ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • 2 Kíróníkà 36
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé 2 Kíróníkà

      • Jèhóáhásì di ọba Júdà (1-3)

      • Jèhóákímù di ọba Júdà (4-8)

      • Jèhóákínì di ọba Júdà (9, 10)

      • Sedekáyà di ọba Júdà (11-14)

      • Ìparun Jerúsálẹ́mù (15-21)

      • Àṣẹ tí Kírúsì pa pé kí wọ́n tún tẹ́ńpìlì kọ́ (22, 23)

2 Kíróníkà 36:1

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Kr 3:15; Jer 22:11
  • +2Ọb 23:30, 31

2 Kíróníkà 36:3

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tálẹ́ńtì kan jẹ́ kìlógíráàmù 34.2. Wo Àfikún B14.

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Ọb 18:14; 23:33

2 Kíróníkà 36:4

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Ọb 23:29; Jer 46:2
  • +2Ọb 23:34; Jer 22:11, 12

2 Kíróníkà 36:5

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jer 26:20, 21; 36:32
  • +2Ọb 23:36, 37

2 Kíróníkà 36:6

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Ọb 24:1; 25:1; Jer 25:1
  • +2Ọb 24:16; Da 1:1

2 Kíróníkà 36:7

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹsr 1:7; Jer 27:16; Da 1:2; 5:2

2 Kíróníkà 36:8

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Ọb 24:5, 6

2 Kíróníkà 36:9

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jer 22:24; Mt 1:12
  • +2Ọb 24:8, 9

2 Kíróníkà 36:10

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ó ṣeé ṣe kó jẹ́, ìgbà ìrúwé.

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Ọb 24:10; Jer 29:1, 2; Isk 1:2
  • +2Ọb 24:13; Jer 27:17, 18
  • +2Ọb 24:17

2 Kíróníkà 36:11

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jer 37:1
  • +2Ọb 24:18-20; Jer 52:1-3

2 Kíróníkà 36:12

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jer 21:1, 2; 34:2; 38:14, 24

2 Kíróníkà 36:13

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “mú ọrùn rẹ̀ le.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Ọb 24:20; Isk 17:12-15

2 Kíróníkà 36:14

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Ọb 16:11; Isk 8:10, 11

2 Kíróníkà 36:16

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Kr 30:1, 10
  • +Jer 5:12
  • +Jer 20:7
  • +Sm 74:1

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Jí!,

    6/8/2003, ojú ìwé 27

2 Kíróníkà 36:17

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “wúńdíá.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Ọb 24:2
  • +Le 26:31; Di 28:25; Sm 79:2
  • +Isk 9:7
  • +Ida 2:21
  • +Di 28:49-51

2 Kíróníkà 36:18

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Ọb 20:16, 17; Ais 39:6; Jer 27:19-22; 52:17

2 Kíróníkà 36:19

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Sm 74:4-7
  • +Jer 52:14
  • +1Ọb 9:7; 2Ọb 25:9, 10; Sm 79:1

2 Kíróníkà 36:20

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ipò ọba.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Ọb 25:21; Sm 137:1
  • +Jer 27:6, 7
  • +Ẹsr 1:1-3

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    “Ete aiyeraiye,” ojú ìwé 128-130

2 Kíróníkà 36:21

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jer 25:9
  • +Le 26:34
  • +Jer 25:12; Sek 1:12

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    11/15/2006, ojú ìwé 32

    “Ete aiyeraiye,” ojú ìwé 128-130

2 Kíróníkà 36:22

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ais 44:28; 45:1
  • +Jer 29:14; 32:42; 33:10, 11
  • +Ẹsr 1:1-4

2 Kíróníkà 36:23

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Da 5:18
  • +Ais 44:28
  • +Ẹsr 7:12, 13

Àwọn míì

2 Kíró. 36:11Kr 3:15; Jer 22:11
2 Kíró. 36:12Ọb 23:30, 31
2 Kíró. 36:32Ọb 18:14; 23:33
2 Kíró. 36:42Ọb 23:29; Jer 46:2
2 Kíró. 36:42Ọb 23:34; Jer 22:11, 12
2 Kíró. 36:5Jer 26:20, 21; 36:32
2 Kíró. 36:52Ọb 23:36, 37
2 Kíró. 36:62Ọb 24:1; 25:1; Jer 25:1
2 Kíró. 36:62Ọb 24:16; Da 1:1
2 Kíró. 36:7Ẹsr 1:7; Jer 27:16; Da 1:2; 5:2
2 Kíró. 36:82Ọb 24:5, 6
2 Kíró. 36:9Jer 22:24; Mt 1:12
2 Kíró. 36:92Ọb 24:8, 9
2 Kíró. 36:102Ọb 24:10; Jer 29:1, 2; Isk 1:2
2 Kíró. 36:102Ọb 24:13; Jer 27:17, 18
2 Kíró. 36:102Ọb 24:17
2 Kíró. 36:11Jer 37:1
2 Kíró. 36:112Ọb 24:18-20; Jer 52:1-3
2 Kíró. 36:12Jer 21:1, 2; 34:2; 38:14, 24
2 Kíró. 36:132Ọb 24:20; Isk 17:12-15
2 Kíró. 36:142Ọb 16:11; Isk 8:10, 11
2 Kíró. 36:162Kr 30:1, 10
2 Kíró. 36:16Jer 5:12
2 Kíró. 36:16Jer 20:7
2 Kíró. 36:16Sm 74:1
2 Kíró. 36:172Ọb 24:2
2 Kíró. 36:17Le 26:31; Di 28:25; Sm 79:2
2 Kíró. 36:17Isk 9:7
2 Kíró. 36:17Ida 2:21
2 Kíró. 36:17Di 28:49-51
2 Kíró. 36:182Ọb 20:16, 17; Ais 39:6; Jer 27:19-22; 52:17
2 Kíró. 36:19Sm 74:4-7
2 Kíró. 36:19Jer 52:14
2 Kíró. 36:191Ọb 9:7; 2Ọb 25:9, 10; Sm 79:1
2 Kíró. 36:202Ọb 25:21; Sm 137:1
2 Kíró. 36:20Jer 27:6, 7
2 Kíró. 36:20Ẹsr 1:1-3
2 Kíró. 36:21Jer 25:9
2 Kíró. 36:21Le 26:34
2 Kíró. 36:21Jer 25:12; Sek 1:12
2 Kíró. 36:22Ais 44:28; 45:1
2 Kíró. 36:22Jer 29:14; 32:42; 33:10, 11
2 Kíró. 36:22Ẹsr 1:1-4
2 Kíró. 36:23Da 5:18
2 Kíró. 36:23Ais 44:28
2 Kíró. 36:23Ẹsr 7:12, 13
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
  • 1
  • 2
  • 3
  • 4
  • 5
  • 6
  • 7
  • 8
  • 9
  • 10
  • 11
  • 12
  • 13
  • 14
  • 15
  • 16
  • 17
  • 18
  • 19
  • 20
  • 21
  • 22
  • 23
Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
2 Kíróníkà 36:1-23

Kíróníkà Kejì

36 Àwọn èèyàn ilẹ̀ náà mú Jèhóáhásì+ ọmọ Jòsáyà, wọ́n sì fi í jọba ní Jerúsálẹ́mù ní ipò bàbá rẹ̀.+ 2 Ẹni ọdún mẹ́tàlélógún (23) ni Jèhóáhásì nígbà tó jọba, oṣù mẹ́ta ló sì fi ṣàkóso ní Jerúsálẹ́mù. 3 Àmọ́, ọba Íjíbítì lé e kúrò lórí oyè ní Jerúsálẹ́mù, ó sì bu owó ìtanràn ọgọ́rùn-ún (100) tálẹ́ńtì* fàdákà àti tálẹ́ńtì wúrà kan lé ilẹ̀ náà.+ 4 Yàtọ̀ síyẹn, ọba Íjíbítì fi Élíákímù arákùnrin Jèhóáhásì jọba lórí Júdà àti Jerúsálẹ́mù, ó sì yí orúkọ rẹ̀ pa dà sí Jèhóákímù; ṣùgbọ́n Nékò+ mú Jèhóáhásì arákùnrin rẹ̀, ó sì mú un wá sí Íjíbítì.+

5 Ẹni ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n (25) ni Jèhóákímù+ nígbà tó jọba, ọdún mọ́kànlá (11) ló sì fi ṣàkóso ní Jerúsálẹ́mù. Ó ń ṣe ohun tó burú ní ojú Jèhófà Ọlọ́run rẹ̀.+ 6 Nebukadinésárì+ ọba Bábílónì wá dojú kọ ọ́, kó lè fi ṣẹkẹ́ṣẹkẹ̀ bàbà méjì dè é láti mú un lọ sí Bábílónì.+ 7 Nebukadinésárì kó lára àwọn nǹkan èlò ilé Jèhófà lọ sí Bábílónì, ó sì kó wọn sínú ààfin rẹ̀ ní Bábílónì.+ 8 Ní ti ìyókù ìtàn Jèhóákímù àti àwọn ohun ìríra tí ó ṣe àti nǹkan búburú tí a mọ̀ nípa rẹ̀, wọ́n wà lákọsílẹ̀ nínú Ìwé Àwọn Ọba Ísírẹ́lì àti ti Júdà; Jèhóákínì ọmọ rẹ̀ sì jọba ní ipò rẹ̀.+

9 Ọmọ ọdún méjìdínlógún (18) ni Jèhóákínì+ nígbà tó jọba, oṣù mẹ́ta àti ọjọ́ mẹ́wàá ló sì fi ṣàkóso ní Jerúsálẹ́mù; ó ń ṣe ohun tó burú ní ojú Jèhófà.+ 10 Ní ìbẹ̀rẹ̀ ọdún,* Ọba Nebukadinésárì ní kí wọ́n lọ mú un wá sí Bábílónì+ pẹ̀lú àwọn ohun iyebíye tó wà ní ilé Jèhófà.+ Bákan náà, ó fi Sedekáyà arákùnrin bàbá rẹ̀ jọba lórí Júdà àti Jerúsálẹ́mù.+

11 Ẹni ọdún mọ́kànlélógún (21) ni Sedekáyà+ nígbà tó jọba, ọdún mọ́kànlá (11) ló sì fi ṣàkóso ní Jerúsálẹ́mù.+ 12 Ó ń ṣe ohun tó burú ní ojú Jèhófà Ọlọ́run rẹ̀. Kò rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀ níwájú wòlíì Jeremáyà,+ ẹni tó ń sọ ohun tí Jèhófà pa láṣẹ fún un. 13 Ó tún ṣọ̀tẹ̀ sí Ọba Nebukadinésárì,+ ẹni tó mú kó fi Ọlọ́run búra, ó ya olórí kunkun* àti ọlọ́kàn líle, ó kọ̀, kò yíjú sí Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì. 14 Gbogbo olórí àwọn àlùfáà àti àwọn èèyàn náà hùwà àìṣòótọ́ tó bùáyà, wọ́n ń ṣe àwọn ohun ìríra tí àwọn orílẹ̀-èdè ń ṣe, wọ́n sì sọ ilé Jèhófà di ẹlẹ́gbin,+ èyí tó ti yà sí mímọ́ ní Jerúsálẹ́mù.

15 Jèhófà Ọlọ́run àwọn baba ńlá wọn ń kìlọ̀ fún wọn nípasẹ̀ àwọn òjíṣẹ́ rẹ̀, ó ń kìlọ̀ fún wọn léraléra, nítorí pé àánú àwọn èèyàn rẹ̀ àti ibùgbé rẹ̀ ń ṣe é. 16 Ṣùgbọ́n wọ́n ń fi àwọn òjíṣẹ́ Ọlọ́run tòótọ́ ṣẹ̀sín,+ wọn ò ka ọ̀rọ̀ rẹ̀ sí,+ wọ́n sì ń fi àwọn wòlíì rẹ̀ ṣe yẹ̀yẹ́,+ títí ìbínú Jèhófà fi ru sí àwọn èèyàn rẹ̀,+ tí ọ̀rọ̀ wọn sì kọjá àtúnṣe.

17 Nítorí náà, ó gbé ọba àwọn ará Kálídíà+ dìde sí wọn, ẹni tó fi idà pa àwọn ọ̀dọ́kùnrin wọn+ nínú ibi mímọ́ wọn;+ kò ṣàánú ọ̀dọ́kùnrin tàbí ọ̀dọ́bìnrin,* arúgbó tàbí aláàárẹ̀.+ Ohun gbogbo ni Ọlọ́run fi lé e lọ́wọ́.+ 18 Gbogbo àwọn nǹkan èlò ilé Ọlọ́run tòótọ́, ńlá àti kékeré pẹ̀lú àwọn ìṣúra ilé Jèhófà àti àwọn ìṣúra ọba àti ti àwọn ìjòyè rẹ̀, gbogbo rẹ̀ pátá ló kó wá sí Bábílónì.+ 19 Ó sun ilé Ọlọ́run tòótọ́ kanlẹ̀,+ ó wó ògiri Jerúsálẹ́mù lulẹ̀,+ ó sun gbogbo àwọn ilé gogoro tó láàbò, ó sì ba gbogbo ohun tó ṣeyebíye jẹ́.+ 20 Ó mú àwọn tó bọ́ lọ́wọ́ idà lẹ́rú, ó kó wọn lọ sí Bábílónì,+ wọ́n sì di ìránṣẹ́ òun+ àti àwọn ọmọ rẹ̀ títí di ìgbà tí ìjọba* Páṣíà fi bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàkóso,+ 21 kí ọ̀rọ̀ tí Jèhófà gbẹnu Jeremáyà sọ lè ṣẹ,+ títí ilẹ̀ náà fi san àwọn sábáàtì rẹ̀ tán.+ Ní gbogbo ọjọ́ tó fi wà ní ahoro, ó ń pa sábáàtì rẹ̀ mọ́, kí àádọ́rin (70) ọdún lè pé.+

22 Ní ọdún kìíní Kírúsì+ ọba Páṣíà, kí ọ̀rọ̀ tí Jèhófà gbẹnu Jeremáyà+ sọ lè ṣẹ, Jèhófà ta ẹ̀mí Kírúsì ọba Páṣíà jí láti kéde ní gbogbo ìjọba rẹ̀, ó sì tún kọ ọ́ sílẹ̀+ pé: 23 “Ohun tí Kírúsì ọba Páṣíà sọ nìyí, ‘Jèhófà Ọlọ́run ọ̀run ti fún mi ní gbogbo ìjọba ayé,+ ó sì pàṣẹ fún mi pé kí n kọ́ ilé fún òun ní Jerúsálẹ́mù, tó wà ní Júdà.+ Ta ni nínú yín tó jẹ́ èèyàn rẹ̀? Kí Jèhófà Ọlọ́run rẹ̀ wà pẹ̀lú rẹ̀, kí ó sì lọ síbẹ̀.’”+

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́