ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • 1 Àwọn Ọba 6
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé 1 Àwọn Ọba

      • Sólómọ́nì kọ́ tẹ́ńpìlì (1-38)

        • Yàrá inú lọ́hùn-ún (19-22)

        • Àwọn kérúbù (23-28)

        • Àwọn ohun gbígbẹ́, àwọn ilẹ̀kùn, àgbàlá inú (29-36)

        • Iṣẹ́ kíkọ́ tẹ́ńpìlì parí ní nǹkan bí ọdún méje (37, 38)

1 Àwọn Ọba 6:1

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Wo Àfikún B15.

  • *

    Wo Àfikún B8.

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 12:14, 51
  • +1Ọb 6:37
  • +1Kr 28:11, 12; 2Kr 3:1, 2

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    “Ete aiyeraiye,” ojú ìwé 120

1 Àwọn Ọba 6:2

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ìgbọ̀nwọ́ kan jẹ́ sẹ̀ǹtímítà 44.5 (ínǹṣì 17.5). Wo Àfikún B14.

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Kr 3:3; Ẹsr 6:3

1 Àwọn Ọba 6:3

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “Gọ̀bì.”

  • *

    Ní Héb., “tẹ́ńpìlì ilé.”

  • *

    Tàbí “fífẹ̀.”

  • *

    Tàbí “ó jẹ́ 20 ìgbọ̀nwọ́ lára fífẹ̀ ilé náà.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Kr 3:4

1 Àwọn Ọba 6:4

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “wíńdò.”

  • *

    Tàbí “Ó ṣe àwọn fèrèsé tó kéré lápá kan tó sì fẹ̀ lódìkejì.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Isk 41:26

1 Àwọn Ọba 6:5

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ibi Mímọ́ ni ibí yìí ń tọ́ka sí.

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Le 16:2; 2Kr 5:7; Heb 9:3
  • +1Ọb 6:10; Isk 41:5, 26

1 Àwọn Ọba 6:6

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ó ṣe àwọn ipele sára.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Isk 41:6, 7

1 Àwọn Ọba 6:7

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Ọb 5:17

1 Àwọn Ọba 6:8

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “lápá ọ̀tún.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Isk 41:11

1 Àwọn Ọba 6:9

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Ọb 6:38
  • +1Ọb 5:6; 6:20

1 Àwọn Ọba 6:10

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Ọb 6:5

1 Àwọn Ọba 6:12

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Di 17:18, 19; 1Ọb 8:25; 1Kr 28:9
  • +2Sa 7:13; 1Kr 22:9

1 Àwọn Ọba 6:13

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 25:8; Le 26:12; Sm 132:13
  • +1Kr 28:20

1 Àwọn Ọba 6:15

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ni Héb., “kọ́.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Ọb 5:8; 2Kr 3:5

1 Àwọn Ọba 6:16

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ìyẹn, nínú ilé náà.

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Kr 3:8, 9; Heb 9:3
  • +1Ọb 6:5

1 Àwọn Ọba 6:17

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ìyẹn, Ibi Mímọ́ tó wà ní iwájú Ibi Mímọ́ Jù Lọ.

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Heb 9:2

1 Àwọn Ọba 6:18

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Ọb 7:24
  • +Ẹk 25:33

1 Àwọn Ọba 6:19

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Heb 9:3
  • +Ẹk 40:21; 1Ọb 8:6

1 Àwọn Ọba 6:20

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Ọb 6:16
  • +Ẹk 30:1; 1Ọb 7:48

1 Àwọn Ọba 6:21

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 26:29; 2Kr 3:7
  • +Ẹk 26:33

1 Àwọn Ọba 6:22

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 30:1, 3; 40:5

1 Àwọn Ọba 6:23

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “igi olóròóró,” ó ṣeé ṣe kó jẹ́ Aleppo pine.

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 3:24; 2Ọb 19:15; Sm 99:1
  • +2Kr 3:10-13; 5:8

1 Àwọn Ọba 6:27

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ìyẹn, Ibi Mímọ́ Jù Lọ.

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Sm 80:1; Ais 37:16; Heb 9:4, 5

1 Àwọn Ọba 6:29

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “yàrá inú àti tòde.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Kr 3:14
  • +Isk 41:17, 18
  • +Ẹk 25:33; 1Ọb 6:18

1 Àwọn Ọba 6:31

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ó ṣeé ṣe kó máa tọ́ka sí fífẹ̀ férémù ilẹ̀kùn tàbí fífẹ̀ àwọn ilẹ̀kùn náà.

1 Àwọn Ọba 6:33

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ibi Mímọ́ ni ibí yìí ń tọ́ka sí.

  • *

    Ó ṣeé ṣe kó máa tọ́ka sí fífẹ̀ férémù ilẹ̀kùn tàbí fífẹ̀ àwọn ilẹ̀kùn náà.

1 Àwọn Ọba 6:34

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Isk 41:24, 25

1 Àwọn Ọba 6:36

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 27:9; 2Kr 4:9; 7:7
  • +1Ọb 7:12

1 Àwọn Ọba 6:37

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Wo Àfikún B15.

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Ọb 6:1

1 Àwọn Ọba 6:38

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Wo Àfikún B15.

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Kr 28:11, 12

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun, ojú ìwé 1697, 1796

Àwọn míì

1 Ọba 6:1Ẹk 12:14, 51
1 Ọba 6:11Ọb 6:37
1 Ọba 6:11Kr 28:11, 12; 2Kr 3:1, 2
1 Ọba 6:22Kr 3:3; Ẹsr 6:3
1 Ọba 6:32Kr 3:4
1 Ọba 6:4Isk 41:26
1 Ọba 6:5Le 16:2; 2Kr 5:7; Heb 9:3
1 Ọba 6:51Ọb 6:10; Isk 41:5, 26
1 Ọba 6:6Isk 41:6, 7
1 Ọba 6:71Ọb 5:17
1 Ọba 6:8Isk 41:11
1 Ọba 6:91Ọb 6:38
1 Ọba 6:91Ọb 5:6; 6:20
1 Ọba 6:101Ọb 6:5
1 Ọba 6:12Di 17:18, 19; 1Ọb 8:25; 1Kr 28:9
1 Ọba 6:122Sa 7:13; 1Kr 22:9
1 Ọba 6:13Ẹk 25:8; Le 26:12; Sm 132:13
1 Ọba 6:131Kr 28:20
1 Ọba 6:151Ọb 5:8; 2Kr 3:5
1 Ọba 6:162Kr 3:8, 9; Heb 9:3
1 Ọba 6:161Ọb 6:5
1 Ọba 6:17Heb 9:2
1 Ọba 6:181Ọb 7:24
1 Ọba 6:18Ẹk 25:33
1 Ọba 6:19Heb 9:3
1 Ọba 6:19Ẹk 40:21; 1Ọb 8:6
1 Ọba 6:201Ọb 6:16
1 Ọba 6:20Ẹk 30:1; 1Ọb 7:48
1 Ọba 6:21Ẹk 26:29; 2Kr 3:7
1 Ọba 6:21Ẹk 26:33
1 Ọba 6:22Ẹk 30:1, 3; 40:5
1 Ọba 6:23Jẹ 3:24; 2Ọb 19:15; Sm 99:1
1 Ọba 6:232Kr 3:10-13; 5:8
1 Ọba 6:27Sm 80:1; Ais 37:16; Heb 9:4, 5
1 Ọba 6:292Kr 3:14
1 Ọba 6:29Isk 41:17, 18
1 Ọba 6:29Ẹk 25:33; 1Ọb 6:18
1 Ọba 6:34Isk 41:24, 25
1 Ọba 6:36Ẹk 27:9; 2Kr 4:9; 7:7
1 Ọba 6:361Ọb 7:12
1 Ọba 6:371Ọb 6:1
1 Ọba 6:381Kr 28:11, 12
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
  • 1
  • 2
  • 3
  • 4
  • 5
  • 6
  • 7
  • 8
  • 9
  • 10
  • 11
  • 12
  • 13
  • 14
  • 15
  • 16
  • 17
  • 18
  • 19
  • 20
  • 21
  • 22
  • 23
  • 24
  • 25
  • 26
  • 27
  • 28
  • 29
  • 30
  • 31
  • 32
  • 33
  • 34
  • 35
  • 36
  • 37
  • 38
Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
1 Àwọn Ọba 6:1-38

Àwọn Ọba Kìíní

6 Ní ọgọ́rùn-ún mẹ́rin ó lé ọgọ́rin (480) ọdún lẹ́yìn tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì jáde kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì,+ ní ọdún kẹrin lẹ́yìn tí Sólómọ́nì di ọba lórí Ísírẹ́lì, ní oṣù Sífì*+ (ìyẹn, oṣù kejì), ó bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ ilé Jèhófà.*+ 2 Ilé tí Ọba Sólómọ́nì kọ́ fún Jèhófà jẹ́ ọgọ́ta (60) ìgbọ̀nwọ́* ní gígùn, ogún (20) ìgbọ̀nwọ́ ní fífẹ̀ àti ọgbọ̀n (30) ìgbọ̀nwọ́ ní gíga.+ 3 Ibi àbáwọlé*+ tó wà níwájú tẹ́ńpìlì* náà jẹ́ ogún (20) ìgbọ̀nwọ́ ní gígùn,* ó sì bá fífẹ̀ ilé náà mu.* Ìgbọ̀nwọ́ mẹ́wàá ló fi yọ síta lára iwájú ilé náà.

4 Ó ṣe àwọn fèrèsé* tí férémù wọn fẹ̀ lápá kan tó sì kéré lódìkejì*+ sí ilé náà. 5 Ó tún mọ ògiri kan ti ògiri ilé náà; ògiri náà yí àwọn ògiri ilé náà ká, ìyẹn ti tẹ́ńpìlì* àti ti yàrá inú lọ́hùn-ún,+ ó sì ṣe àwọn yàrá ẹ̀gbẹ́ sínú rẹ̀ yí ká.+ 6 Àwọn yàrá ẹ̀gbẹ́ tó wà ní ìsàlẹ̀ jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ márùn-ún ní fífẹ̀, ti àárín jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́fà ní fífẹ̀, ti ìkẹta tó sì wà lókè jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ méje ní fífẹ̀, nítorí ó gé àwọn ibì kan sínú lára* ilé náà yí ká, kí ohunkóhun má bàa wọnú ògiri ilé náà.+

7 Àwọn òkúta tí wọ́n ti gbẹ́ sílẹ̀+ ni wọ́n fi kọ́ ilé náà, tí a kò fi gbọ́ ìró òòlù, àáké tàbí ohun èlò irin kankan nínú ilé náà nígbà tí wọ́n ń kọ́ ọ lọ́wọ́. 8 Ẹnu ọ̀nà tó wọ yàrá ẹ̀gbẹ́ tó wà ní ìsàlẹ̀ wà lápá gúúsù* ilé náà,+ àtẹ̀gùn tó yí po ni wọ́n ń gbà gòkè lọ sí yàrá àárín àti láti yàrá àárín dé yàrá kẹta tó wà lókè. 9 Ó kọ́ ilé náà títí ó fi parí rẹ̀,+ ó fi igi kédárì ṣe igi àjà àti pákó+ tó fi bo ilé náà. 10 Ó kọ́ àwọn yàrá ẹ̀gbẹ́ yí ilé náà ká,+ gíga ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ márùn-ún, àwọn gẹdú igi kédárì ni ó sì fi mú wọn mọ́ ara ilé náà.

11 Ní àkókò yìí, Jèhófà bá Sólómọ́nì sọ̀rọ̀, ó ní: 12 “Ní ti ilé tí ò ń kọ́ yìí, tí o bá rìn nínú àwọn òfin mi, tí o pa àwọn ìdájọ́ mi mọ́, tí o pa gbogbo àṣẹ mi mọ́, tí o sì ń rìn nínú wọn,+ èmi náà á mú ìlérí tí mo ṣe fún Dáfídì bàbá rẹ ṣẹ,+ 13 èmi yóò máa gbé láàárín àwọn ọmọ Ísírẹ́lì,+ mi ò sì ní fi àwọn èèyàn mi Ísírẹ́lì+ sílẹ̀.”

14 Sólómọ́nì ń bá iṣẹ́ ilé kíkọ́ náà lọ kí ó lè parí rẹ̀. 15 Ó fi àwọn pátákó kédárì bo* àwọn ògiri inú ilé náà. Ó fi àwọn ẹ̀là gẹdú bo ògiri inú, láti ìsàlẹ̀ ilé náà títí dé àwọn igi ìrólé tó wà ní àjà, ó sì fi àwọn pátákó júnípà+ bo ilẹ̀ ilé náà. 16 Ó fi pátákó kédárì ṣe apá kan tí ó jẹ́ ogún (20) ìgbọ̀nwọ́ sí ẹ̀yìn ilé náà, láti ìsàlẹ̀ ilé náà títí dé àwọn igi ìrólé, ó sì kọ́ Ibi Mímọ́ Jù Lọ+ sínú rẹ̀,* èyí ni yàrá inú lọ́hùn-ún.+ 17 Ogójì (40) ìgbọ̀nwọ́ sì ni apá tó kù níwájú ilé náà, èyí ni tẹ́ńpìlì.*+ 18 Àwọn akèrègbè+ àti ìtànná òdòdó+ ni wọ́n gbẹ́ sára igi kédárì tí ó wà nínú ilé náà. Gbogbo rẹ̀ jẹ́ igi kédárì; kò sí òkúta kankan tí a rí.

19 Ó ṣètò yàrá inú lọ́hùn-ún+ ilé náà kí ó lè gbé àpótí májẹ̀mú Jèhófà síbẹ̀.+ 20 Gígùn yàrá inú lọ́hùn-ún náà jẹ́ ogún (20) ìgbọ̀nwọ́, fífẹ̀ rẹ̀ jẹ́ ogún (20) ìgbọ̀nwọ́, gíga rẹ̀ sì jẹ́ ogún (20) ìgbọ̀nwọ́;+ ó sì fi ògidì wúrà bò ó; ó fi igi kédárì bo pẹpẹ náà.+ 21 Sólómọ́nì fi ògidì wúrà+ bo inú ilé náà, ó na ẹ̀wọ̀n tí wọ́n fi wúrà ṣe sí iwájú yàrá inú lọ́hùn-ún,+ èyí tí wọ́n fi wúrà bò. 22 Ó fi wúrà bo gbogbo ilé náà títí wọ́n fi parí rẹ̀ látòkèdélẹ̀; ó tún fi wúrà bo gbogbo pẹpẹ+ tí ó wà nítòsí yàrá inú lọ́hùn-ún.

23 Nínú yàrá inú lọ́hùn-ún náà, ó fi igi ahóyaya* ṣe kérúbù méjì+ síbẹ̀, gíga ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́wàá.+ 24 Ìyẹ́ apá kan kérúbù náà jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ márùn-ún, ìyẹ́ apá kejì sì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ márùn-ún. Ìgbọ̀nwọ́ mẹ́wàá ni ó jẹ́ láti ṣóńṣó orí ìyẹ́ apá kan dé ṣóńṣó orí ìyẹ́ apá kejì. 25 Kérúbù kejì náà jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́wàá. Àwọn kérúbù méjèèjì rí bákan náà, wọn ò sì tóbi ju ara wọn. 26 Gíga kérúbù àkọ́kọ́ jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́wàá bíi ti kérúbù kejì. 27 Lẹ́yìn náà, ó gbé àwọn kérúbù náà+ sínú yàrá inú lọ́hùn-ún.* Ìyẹ́ apá àwọn kérúbù náà nà jáde tí ó fi jẹ́ pé ìyẹ́ apá kérúbù àkọ́kọ́ kan ògiri kìíní, ìyẹ́ apá kérúbù kejì sì kan ògiri kejì, ìyẹ́ apá àwọn méjèèjì wá kanra ní àárín ilé náà. 28 Ó sì fi wúrà bo àwọn kérúbù náà.

29 Ó gbẹ́ àwòrán àwọn kérúbù,+ igi ọ̀pẹ+ àti ìtànná òdòdó+ sára gbogbo ògiri yàrá méjèèjì* tó wà nínú ilé náà yí ká. 30 Ó fi wúrà bo ilẹ̀ yàrá méjèèjì tó wà nínú ilé náà. 31 Ó fi igi ahóyaya ṣe ilẹ̀kùn ẹnu ọ̀nà yàrá inú lọ́hùn-ún, ó tún fi ṣe àwọn òpó ẹ̀gbẹ̀ẹ̀gbẹ́ àti àwọn òpó ilẹ̀kùn, ó jẹ́ ìdá márùn-ún* ògiri náà. 32 Igi ahóyaya ni wọ́n fi ṣe àwọn ilẹ̀kùn méjèèjì, ó gbẹ́ àwọn kérúbù, igi ọ̀pẹ àti ìtànná òdòdó sára wọn, ó sì fi wúrà bò wọ́n; ó fi òòlù tẹ wúrà náà mọ́ àwọn kérúbù àti àwọn igi ọ̀pẹ náà lára. 33 Bẹ́ẹ̀ náà ni ó ṣe fi igi ahóyaya ṣe férémù ilẹ̀kùn ẹnu ọ̀nà tẹ́ńpìlì,* igun rẹ̀ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin sì dọ́gba.* 34 Ó fi igi júnípà ṣe ilẹ̀kùn méjì. Ilẹ̀kùn àkọ́kọ́ ní awẹ́ méjì tó ṣeé pa dé, ilẹ̀kùn kejì sì ní awẹ́ méjì tó ṣeé pa dé.+ 35 Ó gbẹ́ àwọn kérúbù, igi ọ̀pẹ àti ìtànná òdòdó, ó sì fi wúrà fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ bo gbogbo wọn.

36 Ó fi òkúta gbígbẹ́ kọ́ ipele mẹ́ta ògiri àgbàlá inú,+ lẹ́yìn náà wọ́n gbé ipele kan ìtì igi kédárì+ lé e.

37 Ní ọdún kẹrin, oṣù Sífì,* wọ́n fi ìpìlẹ̀ ilé Jèhófà lélẹ̀;+ 38 ní ọdún kọkànlá, oṣù Búlì* (ìyẹn, oṣù kẹjọ), wọ́n parí gbogbo iṣẹ́ ilé náà bó ṣe wà nínú àwòrán ilé kíkọ́ rẹ̀.+ Torí náà, ọdún méje ni ó fi kọ́ ọ.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́