Sáàmù
Ti Dáfídì.
28 Ìwọ ni mò ń ké pè, Jèhófà, Àpáta+ mi;
Má di etí rẹ sí mi.
2 Gbọ́ ẹ̀bẹ̀ mi nígbà tí mo bá ké pè ọ́ fún ìrànlọ́wọ́
Bí mo ṣe ń gbé ọwọ́ mi sókè sí yàrá inú lọ́hùn-ún ti ibi mímọ́ rẹ.+
3 Má ṣe fà mí lọ pẹ̀lú àwọn ẹni ibi, pẹ̀lú àwọn tó ń ṣe ohun búburú,+
Àwọn tó ń bá ọmọnìkejì wọn sọ̀rọ̀ àlàáfíà, àmọ́ tó jẹ́ pé ibi ló wà lọ́kàn wọn.+
4 San ohun tí wọ́n ṣe pa dà fún wọn,+
Gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ ibi wọn.
San iṣẹ́ ọwọ́ wọn pa dà fún wọn,
Gẹ́gẹ́ bí ohun tí wọ́n ṣe.+
Yóò ya wọ́n lulẹ̀, kò sì ní gbé wọn ró.
6 Ìyìn ni fún Jèhófà,
Torí ó ti gbọ́ ẹ̀bẹ̀ mi fún ìrànlọ́wọ́.
Ó ti ràn mí lọ́wọ́, ọkàn mi sì ń yọ̀,
Torí náà, màá fi orin mi yìn ín.
9 Gba àwọn èèyàn rẹ là, kí o sì bù kún ogún rẹ.+
Máa ṣe olùṣọ́ àgùntàn wọn, kí o sì gbé wọn sí apá rẹ títí láé.+