ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Nọ́ńbà 23
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Nọ́ńbà

      • Báláámù sọ̀rọ̀ lówelówe nígbà àkọ́kọ́ (1-12)

      • Báláámù sọ̀rọ̀ lówelówe nígbà kejì (13-30)

Nọ́ńbà 23:1

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Nọ 22:41

Nọ́ńbà 23:2

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Nọ 23:13, 14, 28-30

Nọ́ńbà 23:4

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Nọ 22:20

Nọ́ńbà 23:5

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Nọ 22:35

Nọ́ńbà 23:7

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Nọ 23:18; 24:3
  • +Jẹ 10:22; Nọ 22:5; Di 23:3, 4
  • +Nọ 22:6

Nọ́ńbà 23:8

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Nọ 22:12

Nọ́ńbà 23:9

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Ọb 8:53
  • +Ẹk 33:16

Nọ́ńbà 23:10

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ọkàn mi.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 13:14, 16; 22:17; Ẹk 1:7

Nọ́ńbà 23:11

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Nọ 24:10; Joṣ 24:10; Ne 13:1, 2

Nọ́ńbà 23:12

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Nọ 22:38; 24:13

Nọ́ńbà 23:13

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Nọ 22:11

Nọ́ńbà 23:14

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Di 34:1
  • +Nọ 22:41; 23:1, 28, 29

Nọ́ńbà 23:16

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Nọ 22:35; 23:5

Nọ́ńbà 23:18

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Nọ 23:7; 24:3

Nọ́ńbà 23:19

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “kábàámọ̀.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Sm 89:35; Tit 1:2
  • +1Sa 15:29
  • +Ais 14:24; 46:10; Mik 7:20

Nọ́ńbà 23:20

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 12:1, 2; 22:15, 17; Nọ 22:12
  • +Nọ 22:18

Nọ́ńbà 23:21

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 13:21; 23:20; 29:45; Ais 8:10

Nọ́ńbà 23:22

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 20:2
  • +Nọ 24:8

Nọ́ńbà 23:23

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 12:1, 3
  • +Nọ 22:7

Nọ́ńbà 23:24

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Nọ 24:9

Nọ́ńbà 23:26

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Nọ 22:38; 23:12

Nọ́ńbà 23:27

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Nọ 23:13

Nọ́ńbà 23:28

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí kó jẹ́, “aṣálẹ̀, aginjù.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Nọ 21:20

Nọ́ńbà 23:29

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Nọ 22:41; 23:1, 14

Àwọn míì

Nọ́ń. 23:1Nọ 22:41
Nọ́ń. 23:2Nọ 23:13, 14, 28-30
Nọ́ń. 23:4Nọ 22:20
Nọ́ń. 23:5Nọ 22:35
Nọ́ń. 23:7Nọ 23:18; 24:3
Nọ́ń. 23:7Jẹ 10:22; Nọ 22:5; Di 23:3, 4
Nọ́ń. 23:7Nọ 22:6
Nọ́ń. 23:8Nọ 22:12
Nọ́ń. 23:91Ọb 8:53
Nọ́ń. 23:9Ẹk 33:16
Nọ́ń. 23:10Jẹ 13:14, 16; 22:17; Ẹk 1:7
Nọ́ń. 23:11Nọ 24:10; Joṣ 24:10; Ne 13:1, 2
Nọ́ń. 23:12Nọ 22:38; 24:13
Nọ́ń. 23:13Nọ 22:11
Nọ́ń. 23:14Di 34:1
Nọ́ń. 23:14Nọ 22:41; 23:1, 28, 29
Nọ́ń. 23:16Nọ 22:35; 23:5
Nọ́ń. 23:18Nọ 23:7; 24:3
Nọ́ń. 23:19Sm 89:35; Tit 1:2
Nọ́ń. 23:191Sa 15:29
Nọ́ń. 23:19Ais 14:24; 46:10; Mik 7:20
Nọ́ń. 23:20Jẹ 12:1, 2; 22:15, 17; Nọ 22:12
Nọ́ń. 23:20Nọ 22:18
Nọ́ń. 23:21Ẹk 13:21; 23:20; 29:45; Ais 8:10
Nọ́ń. 23:22Ẹk 20:2
Nọ́ń. 23:22Nọ 24:8
Nọ́ń. 23:23Jẹ 12:1, 3
Nọ́ń. 23:23Nọ 22:7
Nọ́ń. 23:24Nọ 24:9
Nọ́ń. 23:26Nọ 22:38; 23:12
Nọ́ń. 23:27Nọ 23:13
Nọ́ń. 23:28Nọ 21:20
Nọ́ń. 23:29Nọ 22:41; 23:1, 14
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
  • 1
  • 2
  • 3
  • 4
  • 5
  • 6
  • 7
  • 8
  • 9
  • 10
  • 11
  • 12
  • 13
  • 14
  • 15
  • 16
  • 17
  • 18
  • 19
  • 20
  • 21
  • 22
  • 23
  • 24
  • 25
  • 26
  • 27
  • 28
  • 29
  • 30
Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
Nọ́ńbà 23:1-30

Nọ́ńbà

23 Báláámù wá sọ fún Bálákì pé: “Mọ pẹpẹ+ méje sí ibí yìí, kí o sì ṣètò akọ màlúù méje àti àgbò méje sílẹ̀ fún mi.” 2 Ojú ẹsẹ̀ ni Bálákì ṣe ohun tí Báláámù sọ gẹ́lẹ́. Bálákì àti Báláámù sì fi akọ màlúù kan àti àgbò kan rúbọ lórí pẹpẹ+ kọ̀ọ̀kan. 3 Báláámù wá sọ fún Bálákì pé: “Dúró síbí, nídìí ẹbọ sísun rẹ, èmi á sì lọ. Bóyá Jèhófà máa kàn sí mi. Màá jẹ́ kí o mọ ohunkóhun tó bá fi hàn mí.” Ó wá lọ sórí òkè kan tí ohunkóhun kò hù níbẹ̀.

4 Ọlọ́run kàn sí Báláámù,+ ó sì sọ fún Ọlọ́run pé: “Mo ti to pẹpẹ méje, mo sì ti fi akọ màlúù kan àti àgbò kan rúbọ lórí pẹpẹ kọ̀ọ̀kan.” 5 Jèhófà fi ọ̀rọ̀ yìí sí Báláámù+ lẹ́nu pé: “Pa dà sọ́dọ̀ Bálákì, ohun tí wàá sì sọ fún un nìyí.” 6 Ó wá pa dà, ó sì rí i pé Bálákì àti gbogbo ìjòyè Móábù dúró sí ẹ̀gbẹ́ ẹbọ sísun rẹ̀. 7 Ó wá sọ̀rọ̀ lówelówe pé:+

“Bálákì ọba Móábù mú mi wá láti Árámù,+

Láti àwọn òkè ìlà oòrùn:

‘Wá bá mi gégùn-ún fún Jékọ́bù.

Àní, wá dá Ísírẹ́lì lẹ́bi.’+

 8 Ṣé kí n wá lọ gégùn-ún fún àwọn tí Ọlọ́run ò fi gégùn-ún ni?

Àbí kí n lọ dẹ́bi fún àwọn tí Jèhófà kò dá lẹ́bi?+

 9 Mo rí wọn látorí àwọn àpáta,

Mo sì rí wọn látorí àwọn òkè.

Ibẹ̀ ni wọ́n pàgọ́ sí láwọn nìkan+ bí àwùjọ;

Wọn ò ka ara wọn mọ́ àwọn orílẹ̀-èdè.+

10 Ta ló lè ka àwọn ọmọ Jékọ́bù+ tí wọ́n pọ̀ bí iyanrìn,

Ta ló tiẹ̀ lè ka ìdá mẹ́rin Ísírẹ́lì?

Jẹ́ kí n* kú ikú olódodo,

Sì jẹ́ kí ìgbẹ̀yìn mi rí bíi tiwọn.”

11 Bálákì wá sọ fún Báláámù pé: “Kí lo ṣe sí mi yìí? Mo mú ọ wá kí o lè gégùn-ún fún àwọn ọ̀tá mi, àmọ́ ṣe lo kàn wá ń súre fún wọn.”+ 12 Ó dá a lóhùn pé: “Ṣé kí n má sọ ohun tí Jèhófà bá fi sí mi lẹ́nu+ ni?”

13 Bálákì sọ fún un pé: “Jọ̀ọ́, jẹ́ ká lọ sí ibòmíì tí o ti lè rí wọn. Díẹ̀ nínú wọn ni wàá rí; o ò ní rí gbogbo wọn. Bá mi gégùn-ún fún wọn láti ibẹ̀.”+ 14 Torí náà, ó mú un lọ sí pápá Sófímù, ní orí Písígà,+ ó mọ pẹpẹ méje, ó sì fi akọ màlúù kan àti àgbò kan rúbọ lórí pẹpẹ+ kọ̀ọ̀kan. 15 Báláámù wá sọ fún Bálákì pé: “Dúró síbí, nídìí ẹbọ sísun rẹ, sì jẹ́ kí n kàn sí I níbẹ̀ yẹn.” 16 Jèhófà wá kàn sí Báláámù, ó sì fi ọ̀rọ̀ yìí sí i lẹ́nu+ pé: “Pa dà sọ́dọ̀ Bálákì, ohun tí wàá sì sọ nìyí.” 17 Torí náà, ó wá sọ́dọ̀ rẹ̀, ó sì rí i pé ó dúró ní ẹ̀gbẹ́ ẹbọ sísun rẹ̀, àwọn ìjòyè Móábù sì wà lọ́dọ̀ rẹ̀. Bálákì bi í pé: “Kí ni Jèhófà sọ?” 18 Ó wá sọ̀rọ̀ lówelówe pé:+

“Dìde Bálákì, kí o sì fetí sílẹ̀.

Tẹ́tí sí mi, ìwọ ọmọ Sípórì.

19 Ọlọ́run kì í ṣe èèyàn lásánlàsàn tó máa ń parọ́,+

Tàbí ọmọ èèyàn tó máa ń yí èrò pa dà.*+

Tó bá sọ ohun kan, ṣé kò ní ṣe é?

Tó bá sì sọ̀rọ̀, ǹjẹ́ kò ní mú un ṣẹ?+

20 Wò ó! A ti mú mi wá súre;

Ní báyìí, Ó ti súre,+ mi ò sì lè yí i pa dà.+

21 Kò fàyè gba agbára òkùnkùn èyíkéyìí láti bá Jékọ́bù jà,

Kò sì gbà kí wàhálà kankan dé bá Ísírẹ́lì.

Jèhófà Ọlọ́run rẹ̀ wà pẹ̀lú wọn,+

Wọ́n sì ń pòkìkí rẹ̀ bí ọba láàárín wọn.

22 Ọlọ́run ń mú wọn kúrò ní Íjíbítì.+

Ó dà bí ìwo akọ màlúù igbó fún wọn.+

23 Torí kò sí ẹni tó lè ríran ìparun sí Jékọ́bù,+

Bẹ́ẹ̀ ni ẹnikẹ́ni kò lè woṣẹ́ ibi sí Ísírẹ́lì.+

Ní àkókò yìí, wọ́n á máa sọ nípa Jékọ́bù àti Ísírẹ́lì pé:

‘Ẹ wo ohun tí Ọlọ́run ṣe!’

24 Àwọn èèyàn yìí yóò dìde bíi kìnnìún,

Bíi kìnnìún ni yóò gbé ara rẹ̀ sókè.+

Kò ní dùbúlẹ̀ títí yóò fi jẹ ẹran tó bá mú

Tó sì máa mu ẹ̀jẹ̀ àwọn tó bá pa.”

25 Bálákì wá sọ fún Báláámù pé: “Tó ò bá ti lè gégùn-ún kankan fún un, kò tún yẹ kí o máa súre fún un.” 26 Báláámù fèsì pé: “Ṣebí mo ti sọ fún ọ pé, ‘Gbogbo ohun tí Jèhófà bá sọ ni màá ṣe’?”+

27 Bálákì sọ fún Báláámù pé: “Jọ̀ọ́ tẹ̀ lé mi, jẹ́ kí n tún mú ọ lọ sí ibòmíì. Bóyá Ọlọ́run tòótọ́ máa gbà pé kí o bá mi gégùn-ún fún un láti ibẹ̀.”+ 28 Bálákì wá mú Báláámù lọ sí orí òkè Péórì, tó dojú kọ Jéṣímónì.*+ 29 Báláámù wá sọ fún Bálákì pé: “Mọ pẹpẹ méje sí ibí yìí, kí o sì pèsè akọ màlúù méje àti àgbò méje sílẹ̀ fún mi.”+ 30 Bálákì wá ṣe ohun tí Báláámù sọ gẹ́lẹ́, ó sì fi akọ màlúù kan àti àgbò kan rúbọ lórí pẹpẹ kọ̀ọ̀kan.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́