ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • 2 Kíróníkà 9
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé 2 Kíróníkà

      • Ọbabìnrin Ṣébà wá sọ́dọ̀ Sólómọ́nì (1-12)

      • Ọrọ̀ Sólómọ́nì (13-28)

      • Ikú Sólómọ́nì (29-31)

2 Kíróníkà 9:1

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “àwọn àlọ́.”

  • *

    Tàbí “ẹgbẹ́ abánirìn.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Mt 12:42; Lk 11:31
  • +Sm 72:15
  • +1Ọb 10:1-3

2 Kíróníkà 9:2

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “fara pa mọ́.”

2 Kíróníkà 9:3

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Ọb 3:28; Onw 12:9
  • +1Ọb 10:4-9

2 Kíróníkà 9:4

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “kò sí ẹ̀mí kankan mọ́ nínú rẹ̀.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Ọb 4:22, 23
  • +2Kr 8:12, 13

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    11/1/1999, ojú ìwé 23

2 Kíróníkà 9:5

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ọ̀rọ̀.”

2 Kíróníkà 9:6

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Lk 11:31
  • +Onw 1:16
  • +1Ọb 4:31, 34; 2Kr 1:11, 12

2 Kíróníkà 9:8

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Kr 2:11

2 Kíróníkà 9:9

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tálẹ́ńtì kan jẹ́ kìlógíráàmù 34.2. Wo Àfikún B14.

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Sm 72:10
  • +1Ọb 10:10

2 Kíróníkà 9:10

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Ọb 9:27, 28; 10:22; 2Kr 8:18
  • +1Ọb 10:11, 12

2 Kíróníkà 9:11

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ààfin.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Ọb 6:8
  • +1Ọb 7:1
  • +1Kr 25:1; Sm 92:3

2 Kíróníkà 9:12

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí kó jẹ́, “ní àfikún sí àwọn ẹ̀bùn tí iye rẹ̀ jẹ́.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Ọb 10:13

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    11/1/1999, ojú ìwé 20

2 Kíróníkà 9:13

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Ọb 10:14, 15; 2Kr 1:15; Sm 68:29; 72:15

2 Kíróníkà 9:14

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Sm 72:10

2 Kíróníkà 9:15

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ṣékélì kan jẹ́ gíráàmù 11.4. Wo Àfikún B14.

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Kr 12:9
  • +1Ọb 10:16, 17

2 Kíróníkà 9:16

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Apata kékeré tí àwọn tafàtafà sábà máa ń gbé dání.

  • *

    Mínà kan nínú Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù jẹ́ gíráàmù 570. Wo Àfikún B14.

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Ọb 7:2

2 Kíróníkà 9:17

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Ọb 10:18-20

2 Kíróníkà 9:18

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 49:9

2 Kíróníkà 9:19

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Nọ 23:24

2 Kíróníkà 9:20

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Ọb 10:21, 22, 27

2 Kíróníkà 9:21

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Sm 72:10; Jon 1:3
  • +1Ọb 9:27
  • +1Ọb 10:18

2 Kíróníkà 9:22

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Ọb 3:12, 13; 4:29; 10:23-25

2 Kíróníkà 9:23

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “wá ojú.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Ọb 3:28; 4:34; 2Kr 1:12; Owe 2:6

2 Kíróníkà 9:24

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ọ̀rọ̀ yìí ní Hébérù ń tọ́ka sí ìbaaka.

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Mt 6:29

2 Kíróníkà 9:25

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “àwọn agẹṣin.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Di 17:16; 1Ọb 4:26
  • +1Ọb 10:26

2 Kíróníkà 9:26

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ìyẹn, odò Yúfírétì.

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Ọb 4:21

2 Kíróníkà 9:27

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Ọb 10:27; 1Kr 27:28

2 Kíróníkà 9:28

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Ọb 10:28; 2Kr 1:16

2 Kíróníkà 9:29

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Ọb 11:41-43
  • +2Sa 7:2; 12:1; 1Ọb 1:8; 1Kr 29:29
  • +1Ọb 11:30, 31; 14:2, 6, 10
  • +2Kr 12:15; 13:22
  • +1Ọb 11:26

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    2/15/2012, ojú ìwé 25

2 Kíróníkà 9:31

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Sa 5:9; 1Ọb 2:10
  • +1Ọb 14:21

Àwọn míì

2 Kíró. 9:1Mt 12:42; Lk 11:31
2 Kíró. 9:1Sm 72:15
2 Kíró. 9:11Ọb 10:1-3
2 Kíró. 9:31Ọb 3:28; Onw 12:9
2 Kíró. 9:31Ọb 10:4-9
2 Kíró. 9:41Ọb 4:22, 23
2 Kíró. 9:42Kr 8:12, 13
2 Kíró. 9:6Lk 11:31
2 Kíró. 9:6Onw 1:16
2 Kíró. 9:61Ọb 4:31, 34; 2Kr 1:11, 12
2 Kíró. 9:82Kr 2:11
2 Kíró. 9:9Sm 72:10
2 Kíró. 9:91Ọb 10:10
2 Kíró. 9:101Ọb 9:27, 28; 10:22; 2Kr 8:18
2 Kíró. 9:101Ọb 10:11, 12
2 Kíró. 9:111Ọb 6:8
2 Kíró. 9:111Ọb 7:1
2 Kíró. 9:111Kr 25:1; Sm 92:3
2 Kíró. 9:121Ọb 10:13
2 Kíró. 9:131Ọb 10:14, 15; 2Kr 1:15; Sm 68:29; 72:15
2 Kíró. 9:14Sm 72:10
2 Kíró. 9:152Kr 12:9
2 Kíró. 9:151Ọb 10:16, 17
2 Kíró. 9:161Ọb 7:2
2 Kíró. 9:171Ọb 10:18-20
2 Kíró. 9:18Jẹ 49:9
2 Kíró. 9:19Nọ 23:24
2 Kíró. 9:201Ọb 10:21, 22, 27
2 Kíró. 9:21Sm 72:10; Jon 1:3
2 Kíró. 9:211Ọb 9:27
2 Kíró. 9:211Ọb 10:18
2 Kíró. 9:221Ọb 3:12, 13; 4:29; 10:23-25
2 Kíró. 9:231Ọb 3:28; 4:34; 2Kr 1:12; Owe 2:6
2 Kíró. 9:24Mt 6:29
2 Kíró. 9:25Di 17:16; 1Ọb 4:26
2 Kíró. 9:251Ọb 10:26
2 Kíró. 9:261Ọb 4:21
2 Kíró. 9:271Ọb 10:27; 1Kr 27:28
2 Kíró. 9:281Ọb 10:28; 2Kr 1:16
2 Kíró. 9:291Ọb 11:41-43
2 Kíró. 9:292Sa 7:2; 12:1; 1Ọb 1:8; 1Kr 29:29
2 Kíró. 9:291Ọb 11:30, 31; 14:2, 6, 10
2 Kíró. 9:292Kr 12:15; 13:22
2 Kíró. 9:291Ọb 11:26
2 Kíró. 9:312Sa 5:9; 1Ọb 2:10
2 Kíró. 9:311Ọb 14:21
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
  • 1
  • 2
  • 3
  • 4
  • 5
  • 6
  • 7
  • 8
  • 9
  • 10
  • 11
  • 12
  • 13
  • 14
  • 15
  • 16
  • 17
  • 18
  • 19
  • 20
  • 21
  • 22
  • 23
  • 24
  • 25
  • 26
  • 27
  • 28
  • 29
  • 30
  • 31
Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
2 Kíróníkà 9:1-31

Kíróníkà Kejì

9 Ọbabìnrin Ṣébà+ gbọ́ ìròyìn Sólómọ́nì, torí náà ó wá sí Jerúsálẹ́mù, kó lè fi àwọn ìbéèrè tó ta kókó* dán an wò. Àwọn abọ́barìn* tó gbayì ló tẹ̀ lé e pẹ̀lú àwọn ràkúnmí tó ru òróró básámù àti wúrà tó pọ̀ gan-an+ àti àwọn òkúta iyebíye. Ó lọ sọ́dọ̀ Sólómọ́nì, ó sì bá a sọ gbogbo ohun tó wà lọ́kàn rẹ̀.+ 2 Sólómọ́nì dáhùn gbogbo ìbéèrè rẹ̀. Kò sí ohun tó ṣòro* fún Sólómọ́nì láti ṣàlàyé fún un.

3 Nígbà tí ọbabìnrin Ṣébà rí ọgbọ́n Sólómọ́nì+ àti ilé tó kọ́,+ 4 oúnjẹ orí tábìlì rẹ̀,+ bí àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ ṣe ń jókòó, bó ṣe ṣètò iṣẹ́ àwọn tó ń gbé oúnjẹ fún un àti aṣọ tí wọ́n ń wọ̀, àwọn agbọ́tí rẹ̀ àti aṣọ tí wọ́n ń wọ̀ pẹ̀lú àwọn ẹbọ sísun tó ń rú déédéé ní ilé Jèhófà,+ ẹnu yà á gan-an.* 5 Nítorí náà, ó sọ fún ọba pé: “Òótọ́ ni ìròyìn tí mo gbọ́ ní ilẹ̀ mi nípa àwọn àṣeyọrí* rẹ àti ọgbọ́n rẹ. 6 Àmọ́ mi ò gba ìròyìn náà gbọ́ títí mo fi wá fojú ara mi rí i.+ Wò ó! Ohun tí mo gbọ́ nípa ọ̀pọ̀ ọgbọ́n tí o ní kò tiẹ̀ tó ìdajì rárá.+ O ti ré kọjá àwọn ohun tí mo gbọ́ nípa rẹ.+ 7 Aláyọ̀ ni àwọn èèyàn rẹ, aláyọ̀ sì ni àwọn ìránṣẹ́ rẹ tí wọ́n ń dúró níwájú rẹ nígbà gbogbo, tí wọ́n ń fetí sí ọgbọ́n rẹ! 8 Ìyìn ni fún Jèhófà Ọlọ́run rẹ, ẹni tí inú rẹ̀ dùn sí ọ tó fi gbé ọ gorí ìtẹ́ rẹ̀ láti jẹ́ ọba fún Jèhófà Ọlọ́run rẹ. Torí pé Ọlọ́run rẹ nífẹ̀ẹ́ Ísírẹ́lì,+ ó fi ọ́ jọba lé e lórí láti máa dá ẹjọ́ bó ṣe tọ́ àti láti máa ṣe òdodo, kó lè mú kí Ísírẹ́lì máa wà títí lọ.”

9 Lẹ́yìn náà, ó fún ọba ní ọgọ́fà (120) tálẹ́ńtì* wúrà+ àti òróró básámù tó pọ̀ gan-an àti àwọn òkúta iyebíye. Kò tún sẹ́ni tó kó irú òróró básámù tó pọ̀ wọlé bí èyí tí ọbabìnrin Ṣébà kó wá fún Ọba Sólómọ́nì.+

10 Yàtọ̀ síyẹn, àwọn ìránṣẹ́ Hírámù àti àwọn ìránṣẹ́ Sólómọ́nì tí wọ́n kó wúrà wá láti Ófírì+ tún kó àwọn gẹdú igi álígọ́mù àti àwọn òkúta iyebíye wá.+ 11 Ọba fi àwọn gẹdú igi álígọ́mù náà ṣe àtẹ̀gùn sí ilé Jèhófà+ àti sí ilé* ọba,+ títí kan àwọn háàpù àti àwọn ohun ìkọrin olókùn tín-ín-rín fún àwọn akọrin.+ A kò rí irú àwọn nǹkan yìí rí ní ilẹ̀ Júdà.

12 Ọba Sólómọ́nì náà fún ọbabìnrin Ṣébà ní gbogbo ohun tó fẹ́ àti ohun tó béèrè, ohun tó fún un ju* ohun tó kó wá fún ọba. Lẹ́yìn náà, ó kúrò níbẹ̀, ó sì pa dà sí ilẹ̀ rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀.+

13 Ìwọ̀n wúrà tí wọ́n ń kó wá fún Sólómọ́nì lọ́dọọdún jẹ́ ọgọ́rùn-ún mẹ́fà àti ọgọ́ta ó lé mẹ́fà (666) tálẹ́ńtì wúrà,+ 14 yàtọ̀ sí ohun tí àwọn oníṣòwò àti àwọn ọlọ́jà ń kó wá, títí kan wúrà àti fàdákà tí gbogbo àwọn ọba ará Arébíà àti àwọn gómìnà ilẹ̀ náà ń kó wá fún Sólómọ́nì.+

15 Ọba Sólómọ́nì fi àyọ́pọ̀ wúrà ṣe igba (200) apata ńlá,+ (ọgọ́rùn-ún mẹ́fà [600] ṣékélì* àyọ́pọ̀ wúrà ni ó lò sí ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn),+ 16 ó sì fi àyọ́pọ̀ wúrà ṣe ọgọ́rùn-ún mẹ́ta (300) asà* (wúrà mínà* mẹ́ta ni ó lò sí ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn). Lẹ́yìn náà, ọba kó wọn sínú Ilé Igbó Lẹ́bánónì.+

17 Ọba tún fi eyín erin ṣe ìtẹ́ ńlá kan, ó sì fi ògidì wúrà bò ó.+ 18 Àtẹ̀gùn mẹ́fà ni ìtẹ́ náà ní, àpótí ìtìsẹ̀ tí wọ́n fi wúrà ṣe tún wà lára ìtẹ́ náà, ibi ìgbápálé wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ méjèèjì ìjókòó náà, ère kìnnìún+ kọ̀ọ̀kan sì dúró lẹ́gbẹ̀ẹ́ àwọn ibi ìgbápálé náà. 19 Àwọn kìnnìún+ tó dúró lórí àtẹ̀gùn mẹ́fà náà jẹ́ méjìlá (12), ọ̀kọ̀ọ̀kan wà ní eteetí àtẹ̀gùn kọ̀ọ̀kan. Kò sí ìjọba kankan tó ṣe irú rẹ̀ rí. 20 Gbogbo ohun èlò tí Ọba Sólómọ́nì fi ń mu nǹkan jẹ́ wúrà, gbogbo ohun èlò Ilé Igbó Lẹ́bánónì sì jẹ́ ògidì wúrà. Kò sí ìkankan tí wọ́n fi fàdákà ṣe, nítorí fàdákà kò já mọ́ nǹkan kan nígbà ayé Sólómọ́nì.+ 21 Àwọn ọkọ̀ òkun ọba máa ń lọ sí Táṣíṣì+ pẹ̀lú àwọn ìránṣẹ́ Hírámù.+ Ẹ̀ẹ̀kan lọ́dún mẹ́ta ni àwọn ọkọ̀ òkun Táṣíṣì máa ń kó wúrà àti fàdákà, eyín erin,+ àwọn ìnàkí àti àwọn ẹyẹ ọ̀kín wọlé.

22 Nítorí náà, ọrọ̀ àti ọgbọ́n Ọba Sólómọ́nì pọ̀ ju ti gbogbo àwọn ọba yòókù láyé.+ 23 Àwọn ọba láti ibi gbogbo láyé ń wá sọ́dọ̀* Sólómọ́nì kí wọ́n lè gbọ́ ọgbọ́n tí Ọlọ́run fi sí i lọ́kàn.+ 24 Kálukú wọn ń mú ẹ̀bùn wá, ìyẹn àwọn ohun èlò fàdákà, àwọn ohun èlò wúrà, àwọn aṣọ,+ ìhámọ́ra, òróró básámù, àwọn ẹṣin àti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́,* wọ́n sì ń mú wọn wá lọ́dọọdún. 25 Sólómọ́nì ní ẹgbẹ̀rún mẹ́rin (4,000) ilé ẹṣin fún àwọn ẹṣin àti kẹ̀kẹ́ ẹṣin rẹ̀, ó sì ní ẹgbẹ̀rún méjìlá (12,000) ẹṣin,*+ ó kó wọn sí àwọn ìlú kẹ̀kẹ́ ẹṣin àti sí tòsí ọba ní Jerúsálẹ́mù.+ 26 Ó ṣàkóso gbogbo àwọn ọba láti Odò* títí dé ilẹ̀ àwọn Filísínì àti títí dé ààlà Íjíbítì.+ 27 Ọba mú kí fàdákà tó wà ní Jerúsálẹ́mù pọ̀ rẹpẹtẹ bí òkúta, ó sì mú kí igi kédárì pọ̀ rẹpẹtẹ bí àwọn igi síkámórè tó wà ní Ṣẹ́fẹ́là.+ 28 Wọ́n máa ń kó ẹṣin wá fún Sólómọ́nì láti Íjíbítì+ àti láti gbogbo àwọn ilẹ̀ yòókù.

29 Ní ti ìyókù ìtàn Sólómọ́nì,+ láti ìbẹ̀rẹ̀ dé òpin, ǹjẹ́ kò wà lákọsílẹ̀ nínú ọ̀rọ̀ wòlíì Nátánì,+ nínú àsọtẹ́lẹ̀ Áhíjà+ ọmọ Ṣílò àti nínú àkọsílẹ̀ àwọn ìran Ídò+ aríran tó sọ nípa Jèróbóámù+ ọmọ Nébátì? 30 Sólómọ́nì fi ogójì (40) ọdún jọba ní Jerúsálẹ́mù lórí gbogbo Ísírẹ́lì. 31 Níkẹyìn, Sólómọ́nì sinmi pẹ̀lú àwọn baba ńlá rẹ̀. Nítorí náà, wọ́n sin ín sí Ìlú Dáfídì bàbá rẹ̀;+ Rèhóbóámù ọmọ rẹ̀ sì jọba ní ipò rẹ̀.+

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́