ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Àìsáyà 48
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Àìsáyà

      • Ọlọ́run bá Ísírẹ́lì wí, ó sì wẹ̀ ẹ́ mọ́ (1-11)

      • Jèhófà máa kọ lu Bábílónì (12-16a)

      • Ẹ̀kọ́ Ọlọ́run ṣàǹfààní (16b-19)

      • “Ẹ jáde kúrò ní Bábílónì!” (20-22)

Àìsáyà 48:1

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí kó jẹ́, “ṣẹ̀ wá láti.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 32:28
  • +Di 6:13
  • +Le 19:12; Sef 1:4, 5

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kejì, ojú ìwé 121

Àìsáyà 48:2

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ais 52:1
  • +Jer 21:1, 2

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kejì, ojú ìwé 121

Àìsáyà 48:3

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “àkọ́kọ́.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ais 42:9
  • +Joṣ 21:45; Ais 55:10, 11

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kejì, ojú ìwé 123, 125

Àìsáyà 48:4

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 32:9; 2Ọb 17:13, 14; 2Kr 36:15, 16; Sm 78:8; Isk 3:7

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kejì, ojú ìwé 123-124

Àìsáyà 48:5

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ère dídà.”

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kejì, ojú ìwé 123-124

Àìsáyà 48:6

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ais 43:10
  • +Ais 42:9; 65:17

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kejì, ojú ìwé 123-125

Àìsáyà 48:7

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kejì, ojú ìwé 123-125

Àìsáyà 48:8

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ais 29:10
  • +Jer 5:11; 9:2
  • +Di 9:7; Sm 95:10

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kejì, ojú ìwé 125-126

Àìsáyà 48:9

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Sa 12:22; Sm 25:11; 79:9; Jer 14:7
  • +Ne 9:30, 31; Sm 78:38

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kejì, ojú ìwé 126, 133

Àìsáyà 48:10

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “yẹ̀ ọ́ wò.” Tàbí kó jẹ́, “yàn ọ́.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Owe 17:3
  • +Ais 1:25; Jer 9:7

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kejì, ojú ìwé 126-129

Àìsáyà 48:11

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “Èmi kì í bá ẹnì kankan pín ògo mi.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ais 48:9
  • +Isk 20:9

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kejì, ojú ìwé 126-127

Àìsáyà 48:12

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ais 43:13; 46:4
  • +Ais 44:6; Ifi 1:8; 22:13

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kejì, ojú ìwé 129-130

Àìsáyà 48:13

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Job 38:4
  • +Ais 40:22; 42:5

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kejì, ojú ìwé 129-130

Àìsáyà 48:14

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ais 45:1
  • +Ais 44:28
  • +Ais 13:19; Jer 50:13

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kejì, ojú ìwé 130

Àìsáyà 48:15

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ais 41:2
  • +Ais 45:5

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kejì, ojú ìwé 130

Àìsáyà 48:16

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “pẹ̀lú.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ais 45:19

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kejì, ojú ìwé 130-131

Àìsáyà 48:17

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “fún àǹfààní ara rẹ.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ais 43:14; 44:6; 54:5
  • +1Ọb 8:36; Sm 25:8; Ais 54:13; Mik 4:2
  • +Sm 32:8; Ais 30:20, 21; 49:10

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!, ẹ̀kọ́ 8

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kejì, ojú ìwé 131, 132-134

    Ilé Ìṣọ́,

    3/15/1998, ojú ìwé 17

    2/1/1994, ojú ìwé 13-18

Àìsáyà 48:18

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Di 5:29; Sm 81:13, 14
  • +Sm 119:165; Ais 32:18; 66:12
  • +Emọ 5:23, 24

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!, ẹ̀kọ́ 8

    Ìwé Ìpàdé Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́,

    2/2017, ojú ìwé 2

    ‘Ìfẹ́ Ọlọ́run’, ojú ìwé 198-199

    Ilé Ìṣọ́,

    7/15/2011, ojú ìwé 25

    1/15/2007, ojú ìwé 10

    2/1/1994, ojú ìwé 13-14

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kejì, ojú ìwé 120, 131-134

    Ìmọ̀, ojú ìwé 118

Àìsáyà 48:19

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “èso.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 22:15, 17; Jer 33:22; Ho 1:10

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kejì, ojú ìwé 132

Àìsáyà 48:20

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jer 50:8; Ifi 18:4
  • +Ais 49:13
  • +Jer 50:2
  • +Jer 31:10, 11

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kejì, ojú ìwé 134

    “Kí Ijọba Rẹ Dé,” ojú ìwé 146-147

Àìsáyà 48:21

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 15:24, 25; Di 8:14, 15; Ais 43:19
  • +Ẹk 17:5, 6; Nọ 20:11

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kejì, ojú ìwé 134

Àìsáyà 48:22

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ais 57:20, 21

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kejì, ojú ìwé 135

Àwọn míì

Àìsá. 48:1Jẹ 32:28
Àìsá. 48:1Di 6:13
Àìsá. 48:1Le 19:12; Sef 1:4, 5
Àìsá. 48:2Ais 52:1
Àìsá. 48:2Jer 21:1, 2
Àìsá. 48:3Ais 42:9
Àìsá. 48:3Joṣ 21:45; Ais 55:10, 11
Àìsá. 48:4Ẹk 32:9; 2Ọb 17:13, 14; 2Kr 36:15, 16; Sm 78:8; Isk 3:7
Àìsá. 48:6Ais 43:10
Àìsá. 48:6Ais 42:9; 65:17
Àìsá. 48:8Ais 29:10
Àìsá. 48:8Jer 5:11; 9:2
Àìsá. 48:8Di 9:7; Sm 95:10
Àìsá. 48:91Sa 12:22; Sm 25:11; 79:9; Jer 14:7
Àìsá. 48:9Ne 9:30, 31; Sm 78:38
Àìsá. 48:10Owe 17:3
Àìsá. 48:10Ais 1:25; Jer 9:7
Àìsá. 48:11Ais 48:9
Àìsá. 48:11Isk 20:9
Àìsá. 48:12Ais 43:13; 46:4
Àìsá. 48:12Ais 44:6; Ifi 1:8; 22:13
Àìsá. 48:13Job 38:4
Àìsá. 48:13Ais 40:22; 42:5
Àìsá. 48:14Ais 45:1
Àìsá. 48:14Ais 44:28
Àìsá. 48:14Ais 13:19; Jer 50:13
Àìsá. 48:15Ais 41:2
Àìsá. 48:15Ais 45:5
Àìsá. 48:16Ais 45:19
Àìsá. 48:17Ais 43:14; 44:6; 54:5
Àìsá. 48:171Ọb 8:36; Sm 25:8; Ais 54:13; Mik 4:2
Àìsá. 48:17Sm 32:8; Ais 30:20, 21; 49:10
Àìsá. 48:18Di 5:29; Sm 81:13, 14
Àìsá. 48:18Sm 119:165; Ais 32:18; 66:12
Àìsá. 48:18Emọ 5:23, 24
Àìsá. 48:19Jẹ 22:15, 17; Jer 33:22; Ho 1:10
Àìsá. 48:20Jer 50:8; Ifi 18:4
Àìsá. 48:20Ais 49:13
Àìsá. 48:20Jer 50:2
Àìsá. 48:20Jer 31:10, 11
Àìsá. 48:21Ẹk 15:24, 25; Di 8:14, 15; Ais 43:19
Àìsá. 48:21Ẹk 17:5, 6; Nọ 20:11
Àìsá. 48:22Ais 57:20, 21
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
  • 1
  • 2
  • 3
  • 4
  • 5
  • 6
  • 7
  • 8
  • 9
  • 10
  • 11
  • 12
  • 13
  • 14
  • 15
  • 16
  • 17
  • 18
  • 19
  • 20
  • 21
  • 22
Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
Àìsáyà 48:1-22

Àìsáyà

48 Gbọ́ èyí, ìwọ ilé Jékọ́bù,

Ẹ̀yin tí ẹ̀ ń fi orúkọ Ísírẹ́lì pe ara yín +

Àti ẹ̀yin tí ẹ jáde látinú omi* Júdà,

Ẹ̀yin tí ẹ̀ ń fi orúkọ Jèhófà búra,+

Tí ẹ sì ń ké pe Ọlọ́run Ísírẹ́lì,

Bó tiẹ̀ jẹ́ pé kì í ṣe ní òtítọ́ àti òdodo.+

 2 Torí wọ́n ń fi ìlú mímọ́+ pe ara wọn,

Wọ́n sì ń wá ìtìlẹyìn Ọlọ́run Ísírẹ́lì,+

Tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun.

 3 “Tipẹ́tipẹ́ ni mo ti sọ àwọn ohun àtijọ́* fún ọ.

Wọ́n ti ẹnu mi jáde,

Mo sì jẹ́ kó di mímọ̀.+

Mo gbé ìgbésẹ̀ lójijì, wọ́n sì ṣẹlẹ̀.+

 4 Torí mo mọ bí o ṣe lágídí tó,

Pé irin ni iṣan ọrùn rẹ àti pé bàbà ni iwájú orí rẹ,+

 5 Mo sọ fún ọ tipẹ́tipẹ́.

Kó tó ṣẹlẹ̀, mo mú kí o gbọ́ ọ,

Kí o má bàa sọ pé, ‘Òrìṣà mi ló ṣe èyí,

Ère gbígbẹ́ mi àti ère onírin* mi ló pa á láṣẹ.’

 6 Ẹ ti gbọ́, ẹ sì ti rí gbogbo èyí.

Ṣé ẹ ò ní kéde rẹ̀ ni?+

Láti ìsinsìnyí lọ, màá kéde àwọn ohun tuntun fún ọ,+

Àwọn àṣírí tí mo pa mọ́, tí o kò mọ̀.

 7 A ṣẹ̀ṣẹ̀ dá wọn ni, kì í ṣe látìgbà àtijọ́,

Àwọn ohun tí o ò gbọ́ rí kó tó di òní,

Kí o má bàa sọ pé, ‘Wò ó! Mo ti mọ̀ ọ́n tẹ́lẹ̀.’

 8 Rárá, o ò tíì gbọ́,+ o ò tíì mọ̀ ọ́n,

Etí rẹ ò sì là nígbà àtijọ́.

Nítorí mo mọ̀ pé ọ̀dàlẹ̀ paraku ni ọ́,+

A sì ti pè ọ́ ní ẹlẹ́ṣẹ̀ látìgbà tí wọ́n ti bí ọ.+

 9 Àmọ́ nítorí orúkọ mi, mi ò ní bínú mọ́;+

Nítorí ìyìn mi, màá kó ara mi níjàánu lórí ọ̀rọ̀ rẹ,

Mi ò sì ní pa ọ́ run.+

10 Wò ó! Mo ti yọ́ ọ mọ́, àmọ́ kì í ṣe bíi ti fàdákà.+

Mo ti dán ọ wò* nínú iná ìléru ti ìyà, tí a fi ń yọ́ nǹkan.+

11 Nítorí tèmi, àní nítorí tèmi, màá gbé ìgbésẹ̀,+

Ṣé màá wá jẹ́ kí wọ́n kẹ́gàn mi ni?+

Èmi kì í fi ògo mi fún ẹlòmíì.*

12 Fetí sí mi, ìwọ Jékọ́bù àti ìwọ Ísírẹ́lì, ẹni tí mo ti pè,

Ẹnì kan náà ni mí.+ Èmi ni ẹni àkọ́kọ́; èmi náà ni ẹni ìkẹyìn.+

13 Ọwọ́ mi ni mo fi fi ìpìlẹ̀ ayé sọlẹ̀,+

Ọwọ́ ọ̀tún mi ni mo sì fi na ọ̀run.+

Tí mo bá pè wọ́n, wọ́n jọ máa dìde.

14 Gbogbo yín, ẹ kóra jọ, kí ẹ sì fetí sílẹ̀.

Ta ni nínú wọn ló kéde àwọn nǹkan yìí?

Jèhófà nífẹ̀ẹ́ rẹ̀.+

Ó máa ṣe ohun tó dùn mọ́ ọn nínú sí Bábílónì,+

Apá rẹ̀ sì máa kọ lu àwọn ará Kálídíà.+

15 Èmi fúnra mi ti sọ̀rọ̀, mo sì ti pè é.+

Mo ti mú un wá, ọ̀nà rẹ̀ sì máa yọrí sí rere.+

16 Ẹ sún mọ́ mi, kí ẹ sì gbọ́ èyí.

Láti ìbẹ̀rẹ̀, mi ò sọ̀rọ̀ ní ìkọ̀kọ̀.+

Látìgbà tó ti ṣẹlẹ̀ ni mo ti wà níbẹ̀.”

Ní báyìí, Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ ti rán mi àti* ẹ̀mí rẹ̀.

17 Ohun tí Jèhófà sọ nìyí, Olùtúnrà rẹ, Ẹni Mímọ́ Ísírẹ́lì:+

“Èmi, Jèhófà, ni Ọlọ́run rẹ,

Ẹni tó ń kọ́ ọ kí o lè ṣe ara rẹ láǹfààní,*+

Ẹni tó ń jẹ́ kí o mọ ọ̀nà tó yẹ kí o máa rìn.+

18 Ká ní o fetí sí àwọn àṣẹ mi ni!+

Àlàáfíà rẹ ì bá dà bí odò,+

Òdodo rẹ ì bá sì dà bí ìgbì òkun.+

19 Àwọn ọmọ* rẹ ì bá pọ̀ bí erùpẹ̀ ilẹ̀,

Àwọn àtọmọdọ́mọ rẹ ì bá sì pọ̀ bí iyanrìn.+

A ò ní pa orúkọ wọn rẹ́ tàbí ká pa á run kúrò níwájú mi láé.”

20 Ẹ jáde kúrò ní Bábílónì!+

Ẹ sá kúrò lọ́dọ̀ àwọn ará Kálídíà!

Ẹ fi igbe ayọ̀ polongo rẹ̀! Ẹ kéde rẹ̀!+

Ẹ jẹ́ kó di mímọ̀ dé àwọn ìkángun ayé.+

Ẹ sọ pé: “Jèhófà ti tún Jékọ́bù ìránṣẹ́ rẹ̀ rà.+

21 Òùngbẹ ò gbẹ wọ́n nígbà tó mú wọn gba àwọn ibi tó ti pa run.+

Ó mú kí omi ṣàn jáde látinú àpáta fún wọn;

Ó la àpáta, ó sì mú kí omi rọ́ jáde.”+

22 Jèhófà sọ pé, “Kò sí àlàáfíà fún ẹni burúkú.”+

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́