ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Àìsáyà 66
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Àìsáyà

      • Ìjọsìn tòótọ́ àti ìjọsìn èké (1-6)

      • Síónì tó jẹ́ ìyá àti àwọn ọmọ rẹ̀ (7-17)

      • Àwọn èèyàn kóra jọ láti jọ́sìn ní Jerúsálẹ́mù (18-24)

Àìsáyà 66:1

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Mt 5:34, 35
  • +2Kr 6:18; Iṣe 17:24
  • +1Kr 28:2; Iṣe 7:48-50

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Jíjẹ́rìí Kúnnákúnná, ojú ìwé 49

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kejì, ojú ìwé 390-391

    Ilé Ìṣọ́,

    6/15/1998, ojú ìwé 12

    8/15/1991, ojú ìwé 13

    “Ete aiyeraiye,” ojú ìwé 125

Àìsáyà 66:2

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ṣàníyàn.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ais 40:26
  • +2Ọb 22:18, 19; Lk 18:14

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Jíjẹ́rìí Kúnnákúnná, ojú ìwé 49

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kejì, ojú ìwé 391-392

Àìsáyà 66:3

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí kó jẹ́, “ẹni tó ń ki òrìṣà.”

  • *

    Tàbí “mú ọkàn wọn yọ̀.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ais 1:11
  • +Le 11:27
  • +Di 14:8
  • +Le 2:1, 2
  • +Ais 1:13

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kejì, ojú ìwé 392-393

Àìsáyà 66:4

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Di 28:15
  • +Jer 7:13
  • +2Ọb 21:9; Ais 65:3

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kejì, ojú ìwé 393-394

Àìsáyà 66:5

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ṣàníyàn.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ais 5:18, 19; 29:13
  • +Ais 65:13, 14; Jer 17:13, 18

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kejì, ojú ìwé 394-396

Àìsáyà 66:6

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kejì, ojú ìwé 396-397

Àìsáyà 66:7

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ais 54:1

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kejì, ojú ìwé 397-399

    Ilé-Ìṣọ́nà,

    1/1/1995, ojú ìwé 11

Àìsáyà 66:8

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    11/15/2014, ojú ìwé 26

    11/1/2010, ojú ìwé 27-28

    1/1/1996, ojú ìwé 10

    7/1/1995, ojú ìwé 20-21

    1/1/1995, ojú ìwé 11

    Ìjọba Ọlọ́run Ti Ń Ṣàkóso!, ojú ìwé 233

    Ìparí Ìṣípayá, ojú ìwé 184

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kejì, ojú ìwé 397-399

Àìsáyà 66:9

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kejì, ojú ìwé 399

Àìsáyà 66:10

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ais 44:23
  • +Sm 137:6

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kejì, ojú ìwé 399-400

Àìsáyà 66:11

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kejì, ojú ìwé 399-400

Àìsáyà 66:12

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ais 9:7
  • +Ais 60:3; Hag 2:7

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́ (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́),

    9/2018, ojú ìwé 13-14

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kejì, ojú ìwé 400-401

Àìsáyà 66:13

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ais 51:3
  • +Ais 44:28; 65:18, 19

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́ (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́),

    9/2018, ojú ìwé 13-14

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kejì, ojú ìwé 401

    Ilé-Ìṣọ́nà,

    1/15/1996, ojú ìwé 21-22

Àìsáyà 66:14

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “agbára.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ais 59:18

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kejì, ojú ìwé 401-402

Àìsáyà 66:15

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Di 4:24
  • +Sm 50:3; Jer 25:32, 33
  • +2Tẹ 1:7, 8

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kejì, ojú ìwé 404-405

Àìsáyà 66:16

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “gbogbo èèyàn.”

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kejì, ojú ìwé 404-405

Àìsáyà 66:17

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ìyẹn, àwọn ọgbà tí wọ́n dìídì ṣe fún ìjọsìn òrìṣà.

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ais 1:29; 65:3
  • +Le 11:7, 8; Ais 65:4
  • +Le 11:29

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kejì, ojú ìwé 405-406

Àìsáyà 66:18

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kejì, ojú ìwé 406

Àìsáyà 66:19

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 10:4
  • +Jẹ 10:6, 13
  • +Jẹ 10:2; Isk 27:12, 13
  • +Ais 60:3; Mal 1:11

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kejì, ojú ìwé 406-408

Àìsáyà 66:20

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Di 30:1-3; Ais 11:16; 43:6; 60:4, 9

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kejì, ojú ìwé 408-410

Àìsáyà 66:21

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kejì, ojú ìwé 408, 410

Àìsáyà 66:22

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “èso.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ais 65:17, 18; 2Pe 3:13; Ifi 21:1
  • +Ais 65:23; Jer 31:35, 36

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    10/1/2008, ojú ìwé 8

    4/15/2000, ojú ìwé 14-15

    7/1/1995, ojú ìwé 15

    1/1/1993, ojú ìwé 7-8

    Ìparí Ìṣípayá, ojú ìwé 301

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kejì, ojú ìwé 410-412

Àìsáyà 66:23

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “Gbogbo èèyàn.”

  • *

    Tàbí “jọ́sìn.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Sm 86:9; Sek 14:16; Mal 1:11

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    11/1/2006, ojú ìwé 31

    4/15/2000, ojú ìwé 14-15

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kejì, ojú ìwé 412

Àìsáyà 66:24

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “gbogbo ẹran ara.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ais 34:10; Mt 25:41; Mk 9:47, 48; 2Tẹ 1:9

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    6/15/2008, ojú ìwé 27

    4/15/2000, ojú ìwé 14-15

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kejì, ojú ìwé 414-415

Àwọn míì

Àìsá. 66:1Mt 5:34, 35
Àìsá. 66:12Kr 6:18; Iṣe 17:24
Àìsá. 66:11Kr 28:2; Iṣe 7:48-50
Àìsá. 66:2Ais 40:26
Àìsá. 66:22Ọb 22:18, 19; Lk 18:14
Àìsá. 66:3Ais 1:11
Àìsá. 66:3Le 11:27
Àìsá. 66:3Di 14:8
Àìsá. 66:3Le 2:1, 2
Àìsá. 66:3Ais 1:13
Àìsá. 66:4Di 28:15
Àìsá. 66:4Jer 7:13
Àìsá. 66:42Ọb 21:9; Ais 65:3
Àìsá. 66:5Ais 5:18, 19; 29:13
Àìsá. 66:5Ais 65:13, 14; Jer 17:13, 18
Àìsá. 66:7Ais 54:1
Àìsá. 66:10Ais 44:23
Àìsá. 66:10Sm 137:6
Àìsá. 66:12Ais 9:7
Àìsá. 66:12Ais 60:3; Hag 2:7
Àìsá. 66:13Ais 51:3
Àìsá. 66:13Ais 44:28; 65:18, 19
Àìsá. 66:14Ais 59:18
Àìsá. 66:15Di 4:24
Àìsá. 66:15Sm 50:3; Jer 25:32, 33
Àìsá. 66:152Tẹ 1:7, 8
Àìsá. 66:17Ais 1:29; 65:3
Àìsá. 66:17Le 11:7, 8; Ais 65:4
Àìsá. 66:17Le 11:29
Àìsá. 66:19Jẹ 10:4
Àìsá. 66:19Jẹ 10:6, 13
Àìsá. 66:19Jẹ 10:2; Isk 27:12, 13
Àìsá. 66:19Ais 60:3; Mal 1:11
Àìsá. 66:20Di 30:1-3; Ais 11:16; 43:6; 60:4, 9
Àìsá. 66:22Ais 65:17, 18; 2Pe 3:13; Ifi 21:1
Àìsá. 66:22Ais 65:23; Jer 31:35, 36
Àìsá. 66:23Sm 86:9; Sek 14:16; Mal 1:11
Àìsá. 66:24Ais 34:10; Mt 25:41; Mk 9:47, 48; 2Tẹ 1:9
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
  • 1
  • 2
  • 3
  • 4
  • 5
  • 6
  • 7
  • 8
  • 9
  • 10
  • 11
  • 12
  • 13
  • 14
  • 15
  • 16
  • 17
  • 18
  • 19
  • 20
  • 21
  • 22
  • 23
  • 24
Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
Àìsáyà 66:1-24

Àìsáyà

66 Ohun tí Jèhófà sọ nìyí:

“Ọ̀run ni ìtẹ́ mi, ayé sì ni àpótí ìtìsẹ̀ mi.+

Ilé wo wá ni ẹ lè kọ́ fún mi,+

Ibo sì ni ibi ìsinmi mi?”+

 2 “Ọwọ́ mi ni ó ṣe gbogbo nǹkan yìí,

Bí gbogbo wọn sì ṣe wà nìyí,” ni Jèhófà wí.+

“Màá wá wo ẹni yìí,

Ẹni tó rẹlẹ̀, tí ìbànújẹ́ sì bá ọkàn rẹ̀, tó ń gbọ̀n rìrì* nítorí ọ̀rọ̀ mi.+

 3 Ẹni tó ń pa akọ màlúù dà bí ẹni tó ń ṣá èèyàn balẹ̀.+

Ẹni tó ń fi àgùntàn rúbọ dà bí ẹni tó ń ṣẹ́ ọrùn ajá.+

Ẹni tó ń mú ẹ̀bùn wá dà bí ẹni tó ń fi ẹ̀jẹ̀ ẹlẹ́dẹ̀ rúbọ!+

Ẹni tó ń mú oje igi tùràrí wá láti fi ṣe ọrẹ ìrántí+ dà bí ẹni tó ń fi ọfọ̀ súre.*+

Wọ́n ti yan ọ̀nà tiwọn,

Ohun ìríra ló sì ń múnú wọn dùn.*

 4 Torí náà, màá yan ọ̀nà tí màá fi jẹ wọ́n níyà,+

Àwọn ohun tí wọ́n sì ń bẹ̀rù gan-an ni màá mú kó ṣẹlẹ̀ sí wọn.

Torí nígbà tí mo pè, kò sẹ́ni tó dáhùn;

Nígbà tí mo sọ̀rọ̀, kò sẹ́ni tó fetí sílẹ̀.+

Wọ́n ń ṣe ohun tó burú lójú mi ṣáá,

Ohun tí inú mi ò dùn sí ni wọ́n sì yàn pé àwọn fẹ́ ṣe.”+

 5 Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ Jèhófà, ẹ̀yin tí ẹ̀ ń gbọ̀n rìrì* torí ọ̀rọ̀ rẹ̀:

“Àwọn arákùnrin yín tó kórìíra yín, tí wọ́n sì ta yín nù nítorí orúkọ mi sọ pé, ‘Ká yin Jèhófà lógo!’+

Àmọ́ Ó máa fara hàn, ó sì máa mú ayọ̀ wá fún yín,

Àwọn sì ni ojú máa tì.”+

 6 À ń gbọ́ ariwo látinú ìlú, ìró kan látinú tẹ́ńpìlì!

Ìró Jèhófà ni, ó ń san ohun tó yẹ àwọn ọ̀tá rẹ̀ fún wọn.

 7 Kó tó bẹ̀rẹ̀ sí í rọbí, ó bímọ.+

Kí ìrora ìbímọ tó mú un, ó bí ọmọ ọkùnrin.

 8 Ta ló ti gbọ́ irú rẹ̀ rí?

Ta ló ti rí irú rẹ̀ rí?

Ṣé a lè bí ilẹ̀ kan ní ọjọ́ kan ni?

Àbí a lè bí gbogbo orílẹ̀-èdè kan lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo?

Síbẹ̀, gbàrà tí Síónì bẹ̀rẹ̀ sí í rọbí, ó bí àwọn ọmọkùnrin rẹ̀.

 9 “Ṣé màá mú kó rọbí, tí kò sì ní bímọ ni?” ni Jèhófà wí.

“Àbí máa mú kó bímọ, kí n wá ti ilé ọlẹ̀ rẹ̀ pa?” ni Ọlọ́run rẹ wí.

10 Ẹ bá Jerúsálẹ́mù yọ̀, kí ẹ sì jẹ́ kí inú yín dùn sí i,+ gbogbo ẹ̀yin tí ẹ nífẹ̀ẹ́ rẹ̀.+

Ẹ bá a yọ̀ gidigidi, gbogbo ẹ̀yin tí ẹ̀ ń ṣọ̀fọ̀ rẹ̀,

11 Ẹ máa mu ọmú rẹ̀ tó ń tuni nínú, ó sì máa tẹ́ yín lọ́rùn gidigidi,

Ẹ máa mu ún dáadáa, inú yín sì máa dùn sí ògo rẹ̀ tó pọ̀ rẹpẹtẹ.

12 Nítorí ohun tí Jèhófà sọ nìyí:

“Mò ń nawọ́ àlàáfíà sí i bíi ti odò+

Àti ògo àwọn orílẹ̀-èdè bí àkúnya omi.+

Ẹ máa mu ọmú, a máa gbé yín sí ẹ̀gbẹ́,

Wọ́n á sì máa bá yín ṣeré lórí orúnkún.

13 Bí ìyá ṣe ń tu ọmọ rẹ̀ nínú,

Bẹ́ẹ̀ ni màá máa tù yín nínú;+

Ẹ sì máa rí ìtùnú torí Jerúsálẹ́mù.+

14 Ẹ máa rí èyí, inú yín sì máa dùn,

Egungun yín máa yọ dáadáa bíi koríko tútù.

Àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà máa wá mọ ọwọ́* rẹ̀,

Àmọ́ ó máa dá àwọn ọ̀tá rẹ̀ lẹ́bi.”+

15 “Torí pé Jèhófà máa wá bí iná,+

Àwọn kẹ̀kẹ́ ẹṣin rẹ̀ sì dà bí ìjì líle,+

Láti fi ìbínú líle san ẹ̀san,

Kó sì fi ọwọ́ iná báni wí.+

16 Torí pé iná ni Jèhófà máa fi ṣèdájọ́,

Àní, ó máa fi idà rẹ̀ bá gbogbo ẹran ara* jà;

Àwọn tí Jèhófà pa sì máa pọ̀ rẹpẹtẹ.

17 Àwọn tó ń sọ ara wọn di mímọ́, tí wọ́n sì ń wẹ ara wọn láti wọnú àwọn ọgbà,*+ tí wọ́n ń tẹ̀ lé ẹni tó wà ní àárín, àwọn tó ń jẹ ẹran ẹlẹ́dẹ̀,+ àwọn ohun ìríra àti eku,+ gbogbo wọn jọ máa wá sí òpin wọn,” ni Jèhófà wí. 18 “Torí mo mọ iṣẹ́ wọn àti ìrònú wọn, mò ń bọ̀ wá kó èèyàn gbogbo orílẹ̀-èdè àti èdè jọ, wọ́n sì máa wá rí ògo mi.”

19 “Màá fi àmì kan sáàárín wọn, màá sì rán lára àwọn tó yè bọ́ lọ sí àwọn orílẹ̀-èdè, sí Táṣíṣì,+ Púlì àti Lúdì,+ àwọn tó ń ta ọfà, sí Túbálì àti Jáfánì,+ títí kan àwọn erékùṣù tó wà lọ́nà jíjìn, tí wọn ò tíì gbọ́ ìròyìn nípa mi, tí wọn ò sì tíì rí ògo mi; wọ́n sì máa kéde ògo mi láàárín àwọn orílẹ̀-èdè.+ 20 Wọ́n máa kó gbogbo àwọn arákùnrin yín jáde látinú gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè,+ wọ́n á fi wọ́n ṣe ẹ̀bùn fún Jèhófà, lórí ẹṣin, nínú kẹ̀kẹ́ ẹṣin, nínú kẹ̀kẹ́ tí wọ́n bo orí rẹ̀, lórí àwọn ìbaaka àti lórí àwọn ràkúnmí tó ń yára kánkán, wọ́n á kó wọn wá sórí òkè mímọ́ mi, ìyẹn Jerúsálẹ́mù,” ni Jèhófà wí, “bí ìgbà tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì fi ohun èlò tó mọ́ gbé ẹ̀bùn wọn wá sínú ilé Jèhófà.”

21 “Mo tún máa mú lára wọn láti ṣe àlùfáà, màá sì fi àwọn kan ṣe ọmọ Léfì,” ni Jèhófà wí.

22 “Bí ọ̀run tuntun àti ayé tuntun+ tí mò ń dá ṣe máa dúró níwájú mi,” ni Jèhófà wí, “bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọmọ* yín àti orúkọ yín ṣe máa dúró.”+

23 “Láti òṣùpá tuntun dé òṣùpá tuntun àti láti sábáàtì dé sábáàtì,

Gbogbo ẹran ara* máa wọlé wá tẹrí ba níwájú* mi,”+ ni Jèhófà wí.

24 “Wọ́n á jáde lọ, wọ́n á sì wo òkú àwọn tó ṣọ̀tẹ̀ sí mi;

Torí ìdin ara wọn ò ní kú,

Iná wọn ò ní kú,+

Wọ́n á sì di ohun tó ń kóni nírìíra sí gbogbo èèyàn.”*

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́