ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Ẹ́kísódù 1
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Ẹ́kísódù

      • Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ń pọ̀ sí i ní Íjíbítì (1-7)

      • Fáráò ń fìyà jẹ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì (8-14)

      • Àwọn agbẹ̀bí tó bẹ̀rù Ọlọ́run dá ẹ̀mí sí (15-22)

Ẹ́kísódù 1:1

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 46:8

Ẹ́kísódù 1:2

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Kr 2:3, 4

Ẹ́kísódù 1:4

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 46:17

Ẹ́kísódù 1:5

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ọkàn.”

  • *

    Ní Héb., “tó ti itan Jékọ́bù jáde.”

  • *

    Tàbí “àádọ́rin ọkàn.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 46:26; Di 10:22; Iṣe 7:14

Ẹ́kísódù 1:6

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 50:26

Ẹ́kísódù 1:7

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “Àwọn ọmọkùnrin Ísírẹ́lì.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 46:3; Di 26:5; Iṣe 7:17-19

Ẹ́kísódù 1:9

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Sm 105:24, 25

Ẹ́kísódù 1:11

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “akóniṣiṣẹ́.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 15:13; Ẹk 3:7; Nọ 20:15; Di 26:6
  • +Jẹ 47:11

Ẹ́kísódù 1:12

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 1:7; Sm 105:24, 25

Ẹ́kísódù 1:13

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 2:23; Iṣe 7:6

Ẹ́kísódù 1:14

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Le 26:13

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    3/15/2004, ojú ìwé 25

    6/15/2002, ojú ìwé 8-9

Ẹ́kísódù 1:16

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Isk 16:4

Ẹ́kísódù 1:17

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 9:5, 6

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    11/1/2003, ojú ìwé 8-9

Ẹ́kísódù 1:22

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Iṣe 7:18, 19

Àwọn míì

Ẹ́kís. 1:1Jẹ 46:8
Ẹ́kís. 1:21Kr 2:3, 4
Ẹ́kís. 1:4Jẹ 46:17
Ẹ́kís. 1:5Jẹ 46:26; Di 10:22; Iṣe 7:14
Ẹ́kís. 1:6Jẹ 50:26
Ẹ́kís. 1:7Jẹ 46:3; Di 26:5; Iṣe 7:17-19
Ẹ́kís. 1:9Sm 105:24, 25
Ẹ́kís. 1:11Jẹ 15:13; Ẹk 3:7; Nọ 20:15; Di 26:6
Ẹ́kís. 1:11Jẹ 47:11
Ẹ́kís. 1:12Ẹk 1:7; Sm 105:24, 25
Ẹ́kís. 1:13Ẹk 2:23; Iṣe 7:6
Ẹ́kís. 1:14Le 26:13
Ẹ́kís. 1:16Isk 16:4
Ẹ́kís. 1:17Jẹ 9:5, 6
Ẹ́kís. 1:22Iṣe 7:18, 19
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
  • 1
  • 2
  • 3
  • 4
  • 5
  • 6
  • 7
  • 8
  • 9
  • 10
  • 11
  • 12
  • 13
  • 14
  • 15
  • 16
  • 17
  • 18
  • 19
  • 20
  • 21
  • 22
Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
Ẹ́kísódù 1:1-22

Ẹ́kísódù

1 Orúkọ àwọn ọmọkùnrin Ísírẹ́lì tí wọ́n bá Jékọ́bù wá sí Íjíbítì nìyí, ọkùnrin kọ̀ọ̀kan tó mú agbo ilé rẹ̀ wá:+ 2 Rúbẹ́nì, Síméónì, Léfì àti Júdà;+ 3 Ísákà, Sébúlúnì àti Bẹ́ńjámínì; 4 Dánì àti Náfútálì; Gádì àti Áṣérì.+ 5 Gbogbo ọmọ* tí wọ́n bí fún Jékọ́bù* jẹ́ àádọ́rin (70),* àmọ́ Jósẹ́fù ti wà ní Íjíbítì.+ 6 Lẹ́yìn náà, Jósẹ́fù kú,+ gbogbo àwọn arákùnrin rẹ̀ àti gbogbo ìran yẹn sì kú. 7 Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì* ń bímọ, wọ́n sì ń pọ̀ sí i, wọ́n ń bí sí i, wọ́n sì túbọ̀ ń lágbára gidigidi, débi pé wọ́n kún ilẹ̀ náà.+

8 Nígbà tó yá, ọba tuntun tí kò mọ Jósẹ́fù jẹ ní Íjíbítì. 9 Ó sọ fún àwọn èèyàn rẹ̀ pé: “Ẹ wò ó! Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pọ̀ jù wá lọ, wọ́n sì tún lágbára jù wá lọ.+ 10 Ẹ jẹ́ ká dọ́gbọ́n kan. Àìjẹ́ bẹ́ẹ̀, ṣe ni wọ́n á máa pọ̀ sí i. Tí ogun bá sì dé, wọ́n á dara pọ̀ mọ́ àwọn ọ̀tá wa láti gbógun jà wá, wọ́n á sì kúrò nílùú.”

11 Wọ́n wá yan àwọn ọ̀gá* lé wọn lórí láti máa fipá kó wọn ṣiṣẹ́ àṣekára.+ Wọ́n sì kọ́ àwọn ìlú tí wọ́n ń kó nǹkan pa mọ́ sí fún Fáráò. Orúkọ àwọn ìlú náà ni Pítómù àti Rámísésì.+ 12 Àmọ́ bí wọ́n ṣe ń fìyà jẹ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó ni wọ́n ń pọ̀ sí i, wọ́n sì ń tàn kálẹ̀. Ẹ̀rù àwọn ọmọ Ísírẹ́lì wá ń ba àwọn ará Íjíbítì gidigidi.+ 13 Torí náà, àwọn ará Íjíbítì sọ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì di ẹrú, wọ́n sì ń fìyà jẹ wọ́n gan-an.+ 14 Wọ́n ni wọ́n lára gidigidi bí wọ́n ṣe ń mú wọn ṣiṣẹ́ àṣekára, wọ́n ń fi àpòrọ́ alámọ̀ àti bíríkì ṣiṣẹ́, wọ́n sì ń mú wọn ṣe onírúurú iṣẹ́ nínú oko bí ẹrú. Kódà, wọ́n lò wọ́n nílòkulò bí ẹrú láti ṣe onírúurú iṣẹ́ àṣekára.+

15 Lẹ́yìn náà, ọba Íjíbítì bá àwọn tó ń gbẹ̀bí àwọn Hébérù sọ̀rọ̀, orúkọ wọn ni Ṣífúrà àti Púà, 16 ó sì sọ fún wọn pé: “Tí ẹ bá ń gbẹ̀bí+ àwọn obìnrin Hébérù, tí wọ́n sì wà lórí àpótí ìbímọ, kí ẹ pa ọmọ náà tó bá jẹ́ ọkùnrin; àmọ́ kí ẹ dá ẹ̀mí rẹ̀ sí tó bá jẹ́ obìnrin.” 17 Àmọ́ àwọn agbẹ̀bí náà bẹ̀rù Ọlọ́run tòótọ́, wọn ò sì ṣe ohun tí ọba Íjíbítì ní kí wọ́n ṣe. Ṣe ni wọ́n ń dá ẹ̀mí àwọn ọmọkùnrin sí.+ 18 Nígbà tó yá, ọba Íjíbítì pe àwọn agbẹ̀bí náà, ó sì bi wọ́n pé: “Kí ló dé tí ẹ̀ ń dá ẹ̀mí àwọn ọmọkùnrin sí?” 19 Àwọn agbẹ̀bí náà sọ fún Fáráò pé: “Àwọn obìnrin Hébérù ò dà bí àwọn obìnrin Íjíbítì. Wọ́n lágbára, wọ́n sì ti máa ń bímọ kí agbẹ̀bí tó dé ọ̀dọ̀ wọn.”

20 Ọlọ́run wá ṣojúure sí àwọn agbẹ̀bí náà, àwọn èèyàn náà ń pọ̀ sí i, wọ́n sì ń lágbára sí i. 21 Torí pé àwọn agbẹ̀bí náà bẹ̀rù Ọlọ́run tòótọ́, ó fún wọn ní ìdílé tiwọn nígbà tó yá. 22 Fáráò wá pàṣẹ fún gbogbo èèyàn rẹ̀ pé: “Ẹ ju gbogbo ọmọkùnrin Hébérù tí wọ́n bá ṣẹ̀ṣẹ̀ bí sínú odò Náílì, àmọ́ kí ẹ dá ẹ̀mí gbogbo ọmọbìnrin sí.”+

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́