ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Àìsáyà 24
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Àìsáyà

      • Jèhófà máa sọ ilẹ̀ náà di òfìfo (1-23)

        • Jèhófà di Ọba ní Síónì (23)

Àìsáyà 24:1

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ayé.”

  • *

    Tàbí “Ó ń yí ojú rẹ̀ po.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ais 5:5; Jer 4:6; Isk 6:6
  • +2Ọb 21:13
  • +Di 28:63, 64; Ne 1:8; Jer 9:16

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kìíní, ojú ìwé 260

Àìsáyà 24:2

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Isk 7:12, 13

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kìíní, ojú ìwé 261

Àìsáyà 24:3

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Le 26:31; Di 29:28

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kìíní, ojú ìwé 261

Àìsáyà 24:4

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí kó jẹ́, “gbẹ táútáú.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jer 4:28; Ida 1:4

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kìíní, ojú ìwé 261-263

Àìsáyà 24:5

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “májẹ̀mú àtijọ́.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Le 18:24; Nọ 35:33, 34; 2Kr 33:9; Jer 3:1; 23:10, 11; Ida 4:13
  • +2Ọb 22:13; Da 9:5
  • +Mik 3:11
  • +Ẹk 19:3, 5; 24:7; Jer 31:32; 34:18-20

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kìíní, ojú ìwé 261-263

Àìsáyà 24:6

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Le 26:15, 16
  • +Di 4:27; 28:15, 62

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kìíní, ojú ìwé 261-263

Àìsáyà 24:7

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí kó jẹ́, “gbẹ táútáú.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jer 8:13; Joẹ 1:10
  • +Ais 32:12

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kìíní, ojú ìwé 263-264

Àìsáyà 24:8

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jer 7:34

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kìíní, ojú ìwé 262, 264

Àìsáyà 24:9

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kìíní, ojú ìwé 264

Àìsáyà 24:10

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Ọb 25:8-10

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kìíní, ojú ìwé 264

Àìsáyà 24:11

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ida 5:15

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kìíní, ojú ìwé 264

Àìsáyà 24:12

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ais 32:14; Jer 9:11; Ida 1:4; 2:8, 9

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kìíní, ojú ìwé 264

Àìsáyà 24:13

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ó túmọ̀ sí ṣíṣà lára irè oko tí wọ́n bá fi sílẹ̀.

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Di 24:20
  • +Jer 6:9; Isk 6:8

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    12/1/2006, ojú ìwé 11

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kìíní, ojú ìwé 264-266

Àìsáyà 24:14

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ìwọ̀ oòrùn.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ais 40:9; Jer 31:12; 33:10, 11

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kìíní, ojú ìwé 264-266

Àìsáyà 24:15

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ní ìlà oòrùn.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ais 43:5
  • +Ais 11:11; 60:9

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    12/1/2006, ojú ìwé 11

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kìíní, ojú ìwé 264-266

Àìsáyà 24:16

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “Ẹ ṣe Olódodo lọ́ṣọ̀ọ́!”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 15:11; Ẹsr 9:15; Sm 145:7; Ifi 15:3
  • +Jer 9:2, 3

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kìíní, ojú ìwé 264-267

Àìsáyà 24:17

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jer 8:3; Isk 14:21

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kìíní, ojú ìwé 266-268

Àìsáyà 24:18

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jer 48:44

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kìíní, ojú ìwé 266, 267-268

Àìsáyà 24:19

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jer 4:24

Àìsáyà 24:20

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Ọb 21:16; 2Kr 36:15, 16; Jer 14:20

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kìíní, ojú ìwé 266, 267-268

Àìsáyà 24:21

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    12/1/2006, ojú ìwé 11

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kìíní, ojú ìwé 268-270

Àìsáyà 24:22

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kìíní, ojú ìwé 268-270

Àìsáyà 24:23

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “níwájú àwọn àgbààgbà rẹ̀.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ifi 21:23
  • +Sm 97:1; Ifi 11:17
  • +Sm 132:13; Ais 12:6; Joẹ 3:17; Mik 4:7; Sek 2:10
  • +1Ọb 8:11

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kìíní, ojú ìwé 268-269, 270

Àwọn míì

Àìsá. 24:1Ais 5:5; Jer 4:6; Isk 6:6
Àìsá. 24:12Ọb 21:13
Àìsá. 24:1Di 28:63, 64; Ne 1:8; Jer 9:16
Àìsá. 24:2Isk 7:12, 13
Àìsá. 24:3Le 26:31; Di 29:28
Àìsá. 24:4Jer 4:28; Ida 1:4
Àìsá. 24:5Le 18:24; Nọ 35:33, 34; 2Kr 33:9; Jer 3:1; 23:10, 11; Ida 4:13
Àìsá. 24:52Ọb 22:13; Da 9:5
Àìsá. 24:5Mik 3:11
Àìsá. 24:5Ẹk 19:3, 5; 24:7; Jer 31:32; 34:18-20
Àìsá. 24:6Le 26:15, 16
Àìsá. 24:6Di 4:27; 28:15, 62
Àìsá. 24:7Jer 8:13; Joẹ 1:10
Àìsá. 24:7Ais 32:12
Àìsá. 24:8Jer 7:34
Àìsá. 24:102Ọb 25:8-10
Àìsá. 24:11Ida 5:15
Àìsá. 24:12Ais 32:14; Jer 9:11; Ida 1:4; 2:8, 9
Àìsá. 24:13Di 24:20
Àìsá. 24:13Jer 6:9; Isk 6:8
Àìsá. 24:14Ais 40:9; Jer 31:12; 33:10, 11
Àìsá. 24:15Ais 43:5
Àìsá. 24:15Ais 11:11; 60:9
Àìsá. 24:16Ẹk 15:11; Ẹsr 9:15; Sm 145:7; Ifi 15:3
Àìsá. 24:16Jer 9:2, 3
Àìsá. 24:17Jer 8:3; Isk 14:21
Àìsá. 24:18Jer 48:44
Àìsá. 24:19Jer 4:24
Àìsá. 24:202Ọb 21:16; 2Kr 36:15, 16; Jer 14:20
Àìsá. 24:23Ifi 21:23
Àìsá. 24:23Sm 97:1; Ifi 11:17
Àìsá. 24:23Sm 132:13; Ais 12:6; Joẹ 3:17; Mik 4:7; Sek 2:10
Àìsá. 24:231Ọb 8:11
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
  • 1
  • 2
  • 3
  • 4
  • 5
  • 6
  • 7
  • 8
  • 9
  • 10
  • 11
  • 12
  • 13
  • 14
  • 15
  • 16
  • 17
  • 18
  • 19
  • 20
  • 21
  • 22
  • 23
Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
Àìsáyà 24:1-23

Àìsáyà

24 Wò ó! Jèhófà máa sọ ilẹ̀ náà* di òfìfo, ó sì máa sọ ọ́ di ahoro.+

Ó ń dojú rẹ̀ dé,*+ ó sì ń tú àwọn tó ń gbé inú rẹ̀ ká.+

 2 Bákan náà ló máa rí fún gbogbo èèyàn:

Àwọn èèyàn àti àlùfáà,

Ìránṣẹ́kùnrin àti ọ̀gá rẹ̀ ọkùnrin,

Ìránṣẹ́bìnrin àti ọ̀gá rẹ̀ obìnrin,

Ẹni tó ń rà àti ẹni tó ń tà,

Ẹni tó ń yáni ní nǹkan àti ẹni tó ń yá nǹkan,

Ẹni tó ń yáni lówó àti ẹni tó ń yáwó.+

 3 Wọ́n máa mú kí ilẹ̀ náà ṣófo pátápátá;

Wọ́n máa kó gbogbo ẹrù rẹ̀,+

Torí Jèhófà ti sọ ọ̀rọ̀ yìí.

 4 Ilẹ̀ náà ń ṣọ̀fọ̀;*+ ó ń joro.

Ilẹ̀ tó ń méso jáde ò lọ́ràá mọ́; ó ti ń ṣá.

Àwọn gbajúmọ̀ ilẹ̀ náà ti rẹ̀ dà nù.

 5 Àwọn tó ń gbé ilẹ̀ náà ti ba ibẹ̀ jẹ́,+

Torí wọ́n ti rú òfin,+

Wọ́n ti yí ìlànà pa dà,+

Wọ́n sì da májẹ̀mú tó wà pẹ́ títí.*+

 6 Ìdí nìyẹn tí ègún fi jẹ ilẹ̀ náà run,+

Tí a sì dẹ́bi fún àwọn tó ń gbé ibẹ̀.

Ìdí nìyẹn tí àwọn tó ń gbé ilẹ̀ náà fi dín kù,

Àwọn tó sì ṣẹ́ kù níbẹ̀ ò pọ̀ rárá.+

 7 Wáìnì tuntun ń ṣọ̀fọ̀,* àjàrà rọ,+

Gbogbo àwọn tí inú wọn sì ń dùn ń kẹ́dùn.+

 8 Ayọ̀ ìlù tanboríìnì ti dáwọ́ dúró;

Ariwo àwọn tó ń ṣe àríyá ti dópin;

Ìró ayọ̀ háàpù ti dáwọ́ dúró.+

 9 Wọ́n ń mu wáìnì láìsí orin,

Ọtí sì ń korò lẹ́nu àwọn tó ń mu ún.

10 Ìlú tí wọ́n pa tì ti wó lulẹ̀;+

Gbogbo ilé wà ní títì pa kí ẹnikẹ́ni má bàa wọlé.

11 Wọ́n ń kígbe ní àwọn ojú ọ̀nà torí wáìnì.

Gbogbo ìdùnnú ti pòórá;

Ayọ̀ ilẹ̀ náà ti lọ.+

12 Wọ́n fi ìlú náà sílẹ̀ ní àwókù;

Wọ́n ti wó ẹnubodè wómúwómú, ó ti di òkìtì àwókù.+

13 Bó ṣe máa rí ní ilẹ̀ náà nìyí, láàárín àwọn èèyàn náà:

Bí ìgbà tí wọ́n bá lu igi ólífì,+

Bí ìgbà tí wọ́n pèéṣẹ́* nígbà tí ìkórè èso àjàrà dópin.+

14 Wọ́n máa gbóhùn sókè,

Wọ́n máa kígbe ayọ̀.

Wọ́n máa kéde títóbi Jèhófà láti òkun.*+

15 Ìdí nìyẹn tí wọ́n fi máa yin Jèhófà lógo ní agbègbè ìmọ́lẹ̀;*+

Ní àwọn erékùṣù òkun, wọ́n máa yin orúkọ Jèhófà, Ọlọ́run Ísírẹ́lì lógo.+

16 À ń gbọ́ àwọn orin láti ìkángun ayé pé:

“Ògo ni fún Olódodo!”*+

Àmọ́ mo sọ pé: “Mò ń kú lọ, mò ń kú lọ!

Ó mà ṣe fún mi o! Àwọn ọ̀dàlẹ̀ ti dalẹ̀;

Ìwà ọ̀dàlẹ̀ wọn ni àwọn ọ̀dàlẹ̀ fi dalẹ̀.”+

17 Ìbẹ̀rù, kòtò àti pańpẹ́ ń dúró dè ọ́, ìwọ tó ń gbé ilẹ̀ náà.+

18 Ẹnikẹ́ni tó bá ń sá fún ìró ìbẹ̀rù á já sínú kòtò,

Pańpẹ́ sì máa mú ẹnikẹ́ni tó bá ń jáde látinú kòtò.+

Torí àwọn ibú omi ọ̀run máa ṣí,

Àwọn ìpìlẹ̀ ilẹ̀ sì máa mì tìtì.

19 Ilẹ̀ náà ti fọ́ sọ́tọ̀ọ̀tọ̀;

A ti mi ilẹ̀ náà jìgìjìgì;

Ilẹ̀ náà ń gbọ̀n rìrì.+

20 Ilẹ̀ náà ń ta gọ̀ọ́gọ̀ọ́ bí ẹni tó mutí yó,

Ó sì ń fì síwá sẹ́yìn bí ahéré nínú afẹ́fẹ́.

Ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ wà lórí rẹ̀, ó sì wúwo gan-an,+

Ó máa ṣubú, débi pé kò ní dìde mọ́.

21 Ní ọjọ́ yẹn, Jèhófà máa yíjú sí àwọn ọmọ ogun ibi gíga lókè

Àti sí àwọn ọba ayé lórí ilẹ̀.

22 A máa kó wọn jọ

Bí àwọn ẹlẹ́wọ̀n tí wọ́n kó jọ sínú kòtò,

A máa tì wọ́n pa mọ́ inú àjà ilẹ̀;

Lẹ́yìn ọ̀pọ̀ ọjọ́, a máa rántí wọn.

23 Òṣùpá àrànmọ́jú máa tẹ́,

Ojú sì máa ti oòrùn tó ń ràn,+

Torí Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun ti di Ọba+ ní Òkè Síónì+ àti ní Jerúsálẹ́mù,

Ògo rẹ̀ ń tàn níwájú àwọn àgbààgbà àwọn èèyàn rẹ̀.*+

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́