ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Ìsíkíẹ́lì 33
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Ìsíkíẹ́lì

      • Iṣẹ́ olùṣọ́ (1-20)

      • Ìròyìn ìparun Jerúsálẹ́mù (21, 22)

      • Ọlọ́run rán ẹnì kan sí àwọn tó ń gbé inú àwókù (23-29)

      • Àwọn èèyàn ò ṣe ohun tí wọ́n gbọ́ (30-33)

        • Ìsíkíẹ́lì “dà bí orin ìfẹ́” (32)

        • “Wòlíì kan ti wà láàárín wọn” (33)

Ìsíkíẹ́lì 33:2

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Isk 3:11
  • +Le 26:25; Isk 6:3; 21:9

Ìsíkíẹ́lì 33:3

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jer 4:5; Ho 8:1

Ìsíkíẹ́lì 33:4

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “tó sì mú un lọ.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jer 6:17; Sek 1:4
  • +Isk 3:19; Iṣe 18:6

Ìsíkíẹ́lì 33:5

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ọkàn.”

Ìsíkíẹ́lì 33:6

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ọkàn.”

  • *

    Tàbí “ọrùn olùṣọ́ náà ni màá ka ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ sí.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ais 56:10
  • +Isk 3:18

Ìsíkíẹ́lì 33:7

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ais 21:8; Jer 1:17; Isk 3:17

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ìjọsìn Mímọ́, ojú ìwé 122, 125-126

Ìsíkíẹ́lì 33:8

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ais 3:11; Isk 18:4
  • +Owe 11:21

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ìjọsìn Mímọ́, ojú ìwé 122

Ìsíkíẹ́lì 33:9

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ọkàn.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Owe 15:10
  • +Isk 3:19; Iṣe 18:6

Ìsíkíẹ́lì 33:10

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Le 26:39; Ais 64:6; Isk 24:23
  • +Isk 37:11

Ìsíkíẹ́lì 33:11

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Isk 18:23; 1Ti 2:3, 4
  • +Ais 31:6; Lk 15:10
  • +Sm 130:7, 8
  • +Ais 55:7; Jer 3:22; 25:5; Iṣe 3:19
  • +Isk 18:31; 2Pe 3:9

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!, ẹ̀kọ́ 57

Ìsíkíẹ́lì 33:12

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Isk 3:20; 18:24
  • +1Ọb 8:48, 50; Isk 18:21
  • +Isk 18:26

Ìsíkíẹ́lì 33:13

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “tí kò sì ṣe òdodo.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Pe 2:20
  • +Isk 18:4

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ìjọsìn Mímọ́, ojú ìwé 122, 124-125

Ìsíkíẹ́lì 33:14

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ais 55:7; Isk 18:21; Mik 6:8

Ìsíkíẹ́lì 33:15

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 22:26
  • +Le 6:2, 4; Isk 22:29
  • +Le 18:5; Isk 18:27

Ìsíkíẹ́lì 33:16

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “rántí ẹ̀ṣẹ̀ tó ti dá.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ais 1:18
  • +Isk 20:11

Ìsíkíẹ́lì 33:18

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Heb 10:38; 2Pe 2:20

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ìjọsìn Mímọ́, ojú ìwé 122

Ìsíkíẹ́lì 33:19

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Isk 18:27

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ìjọsìn Mímọ́, ojú ìwé 122

Ìsíkíẹ́lì 33:20

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Isk 18:25, 29

Ìsíkíẹ́lì 33:21

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Isk 24:25-27
  • +2Ọb 25:4; 2Kr 36:17; Jer 39:2

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ìjọsìn Mímọ́, ojú ìwé 112

Ìsíkíẹ́lì 33:22

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Isk 3:26

Ìsíkíẹ́lì 33:24

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jer 39:10; Isk 36:4
  • +Jẹ 12:7

Ìsíkíẹ́lì 33:25

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ó ṣeé ṣe kí ọ̀rọ̀ Hébérù yìí ní í ṣe pẹ̀lú ọ̀rọ̀ tí wọ́n ń lò fún “ìgbẹ́,” wọ́n sì máa ń lò ó fún ohun tí wọ́n bá kórìíra.

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 9:4; Le 17:12
  • +Isk 22:6

Ìsíkíẹ́lì 33:26

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Sef 3:3
  • +Jer 5:8
  • +Di 4:26; Joṣ 23:15

Ìsíkíẹ́lì 33:27

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jer 42:22; Isk 5:12

Ìsíkíẹ́lì 33:28

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Kr 36:20, 21; Ais 6:11; Jer 44:2
  • +Isk 6:3

Ìsíkíẹ́lì 33:29

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jer 9:11; 25:11
  • +2Ọb 17:9; 2Kr 36:14

Ìsíkíẹ́lì 33:30

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jer 18:18

Ìsíkíẹ́lì 33:31

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “sọ̀rọ̀ ìfẹ́ orí ahọ́n.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ais 29:13; Jer 44:16, 17

Ìsíkíẹ́lì 33:33

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Isk 2:5

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé-Ìṣọ́nà,

    3/15/1991, ojú ìwé 17

Àwọn míì

Ìsík. 33:2Isk 3:11
Ìsík. 33:2Le 26:25; Isk 6:3; 21:9
Ìsík. 33:3Jer 4:5; Ho 8:1
Ìsík. 33:4Jer 6:17; Sek 1:4
Ìsík. 33:4Isk 3:19; Iṣe 18:6
Ìsík. 33:6Ais 56:10
Ìsík. 33:6Isk 3:18
Ìsík. 33:7Ais 21:8; Jer 1:17; Isk 3:17
Ìsík. 33:8Ais 3:11; Isk 18:4
Ìsík. 33:8Owe 11:21
Ìsík. 33:9Owe 15:10
Ìsík. 33:9Isk 3:19; Iṣe 18:6
Ìsík. 33:10Le 26:39; Ais 64:6; Isk 24:23
Ìsík. 33:10Isk 37:11
Ìsík. 33:11Isk 18:23; 1Ti 2:3, 4
Ìsík. 33:11Ais 31:6; Lk 15:10
Ìsík. 33:11Sm 130:7, 8
Ìsík. 33:11Ais 55:7; Jer 3:22; 25:5; Iṣe 3:19
Ìsík. 33:11Isk 18:31; 2Pe 3:9
Ìsík. 33:12Isk 3:20; 18:24
Ìsík. 33:121Ọb 8:48, 50; Isk 18:21
Ìsík. 33:12Isk 18:26
Ìsík. 33:132Pe 2:20
Ìsík. 33:13Isk 18:4
Ìsík. 33:14Ais 55:7; Isk 18:21; Mik 6:8
Ìsík. 33:15Ẹk 22:26
Ìsík. 33:15Le 6:2, 4; Isk 22:29
Ìsík. 33:15Le 18:5; Isk 18:27
Ìsík. 33:16Ais 1:18
Ìsík. 33:16Isk 20:11
Ìsík. 33:18Heb 10:38; 2Pe 2:20
Ìsík. 33:19Isk 18:27
Ìsík. 33:20Isk 18:25, 29
Ìsík. 33:21Isk 24:25-27
Ìsík. 33:212Ọb 25:4; 2Kr 36:17; Jer 39:2
Ìsík. 33:22Isk 3:26
Ìsík. 33:24Jer 39:10; Isk 36:4
Ìsík. 33:24Jẹ 12:7
Ìsík. 33:25Jẹ 9:4; Le 17:12
Ìsík. 33:25Isk 22:6
Ìsík. 33:26Sef 3:3
Ìsík. 33:26Jer 5:8
Ìsík. 33:26Di 4:26; Joṣ 23:15
Ìsík. 33:27Jer 42:22; Isk 5:12
Ìsík. 33:282Kr 36:20, 21; Ais 6:11; Jer 44:2
Ìsík. 33:28Isk 6:3
Ìsík. 33:29Jer 9:11; 25:11
Ìsík. 33:292Ọb 17:9; 2Kr 36:14
Ìsík. 33:30Jer 18:18
Ìsík. 33:31Ais 29:13; Jer 44:16, 17
Ìsík. 33:33Isk 2:5
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
  • 1
  • 2
  • 3
  • 4
  • 5
  • 6
  • 7
  • 8
  • 9
  • 10
  • 11
  • 12
  • 13
  • 14
  • 15
  • 16
  • 17
  • 18
  • 19
  • 20
  • 21
  • 22
  • 23
  • 24
  • 25
  • 26
  • 27
  • 28
  • 29
  • 30
  • 31
  • 32
  • 33
Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
Ìsíkíẹ́lì 33:1-33

Ìsíkíẹ́lì

33 Jèhófà bá mi sọ̀rọ̀, ó ní: 2 “Ọmọ èèyàn, bá àwọn ọmọ èèyàn rẹ sọ̀rọ̀,+ kí o sì sọ fún wọn pé,

“‘Ká sọ pé mo mú idà wá sórí ilẹ̀ kan,+ tí gbogbo èèyàn ilẹ̀ náà mú ọkùnrin kan, tí wọ́n sì fi ṣe olùṣọ́ wọn, 3 tó sì rí idà tó ń bọ̀ wá sórí ilẹ̀ náà, tó fun ìwo, tó sì kìlọ̀ fún àwọn èèyàn.+ 4 Tí ẹnì kan bá gbọ́ tí ìwo dún àmọ́ tí kò fetí sí ìkìlọ̀,+ tí idà wá, tó sì gba ẹ̀mí rẹ̀,* ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ yóò wà ní ọrùn òun fúnra rẹ̀.+ 5 Ó gbọ́ tí ìwo dún, àmọ́ kò gba ìkìlọ̀. Ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ yóò wà ní ọrùn rẹ̀. Ká ní ó gba ìkìlọ̀ ni, ì bá gba ẹ̀mí* ara rẹ̀ là.

6 “‘Àmọ́ tí olùṣọ́ náà bá rí i pé idà ń bọ̀, tí kò fun ìwo,+ tí àwọn èèyàn kò sì rí ìkìlọ̀ gbà, tí idà sì dé, tó sì gba ẹ̀mí* ẹnì kan nínú wọn, ẹni yẹn á kú nítorí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, àmọ́ màá béèrè ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ lọ́wọ́ olùṣọ́ náà.’*+

7 “Ní tìrẹ, ọmọ èèyàn, mo ti fi ọ́ ṣe olùṣọ́ fún ilé Ísírẹ́lì, nígbà tí o bá gbọ́ ọ̀rọ̀ ẹnu mi, kí o bá mi kìlọ̀ fún wọn.+ 8 Tí mo bá sọ fún ẹni burúkú pé, ‘Ìwọ ẹni burúkú, ó dájú pé wàá kú!’+ àmọ́ tí ìwọ kò sọ ohunkóhun láti kìlọ̀ fún ẹni burúkú náà pé kó yí ìwà rẹ̀ pa dà, ẹni burúkú náà yóò kú nítorí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀,+ àmọ́ ọwọ́ rẹ ni màá ti béèrè ẹ̀jẹ̀ rẹ̀. 9 Àmọ́ tí o bá kìlọ̀ fún ẹni burúkú pé kó yí ìwà rẹ̀ pa dà tí kò sì yí pa dà, ẹni burúkú náà yóò kú torí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀,+ ṣùgbọ́n ó dájú pé ìwọ yóò gba ẹ̀mí* rẹ là.+

10 “Ìwọ ọmọ èèyàn, sọ fún ilé Ísírẹ́lì pé, ‘O ti sọ pé: “Ọ̀tẹ̀ wa àti ẹ̀ṣẹ̀ wa ti dẹ́rù pa wá, ó ń mú kó rẹ̀ wá;+ báwo la ṣe máa wá wà láàyè?”’+ 11 Sọ fún wọn pé, ‘“Bí mo ti wà láàyè,” ni Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí, “inú mi ò dùn sí ikú ẹni burúkú,+ bí kò ṣe pé kí ẹni burúkú yí ìwà rẹ̀ pa dà,+ kó sì máa wà láàyè.+ Ẹ yí pa dà, ẹ yí ìwà búburú yín pa dà,+ ṣé ó wá yẹ kí ẹ kú ni, ilé Ísírẹ́lì?”’+

12 “Ìwọ ọmọ èèyàn, sọ fún àwọn ọmọ èèyàn rẹ pé, ‘Bí olódodo bá ṣọ̀tẹ̀, òdodo rẹ̀ kò ní gbà á là;+ bẹ́ẹ̀ sì ni ìwà burúkú ẹni burúkú kò ní mú kó kọsẹ̀ nígbà tó bá fi ìwà búburú rẹ̀ sílẹ̀;+ olódodo kò sì ní lè máa wà láàyè nítorí òdodo rẹ̀ lọ́jọ́ tó bá dẹ́ṣẹ̀.+ 13 Tí mo bá sọ fún olódodo pé: “Ó dájú pé ìwọ yóò máa wà láàyè,” tó wá gbẹ́kẹ̀ lé òdodo rẹ̀, tó sì wá ń ṣe ohun tí kò dáa,*+ mi ò ní rántí ìkankan nínú iṣẹ́ òdodo rẹ̀, àmọ́ yóò kú torí ohun tí kò dáa tó ṣe.+

14 “‘Tí mo bá sì sọ fún ẹni burúkú pé: “Ó dájú pé wàá kú,” tó wá fi ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ sílẹ̀, tó sì ń ṣe ohun tó tọ́ àti ohun tó jẹ́ òdodo,+ 15 tí ẹni burúkú náà wá dá ohun tí wọ́n fi ṣe ìdúró pa dà,+ tó dá àwọn nǹkan tó jí pa dà,+ tó ń hùwà tó dáa láti fi hàn pé òun ń tẹ̀ lé àṣẹ tó ń fúnni ní ìyè, ó dájú pé yóò máa wà láàyè.+ Kò ní kú. 16 Èmi kò ní ka èyíkéyìí nínú ẹ̀ṣẹ̀ tó ti dá sí i lọ́rùn.*+ Ó dájú pé yóò máa wà láàyè torí ó ṣe ohun tó tọ́, ó sì ṣe òdodo.’+

17 “Àmọ́ àwọn èèyàn rẹ sọ pé, ‘Ọ̀nà Jèhófà kò tọ́,’ nígbà tó jẹ́ pé ọ̀nà tiwọn ni kò tọ́.

18 “Tí olódodo bá fi òdodo tó ń ṣe sílẹ̀, tó sì wá ń ṣe ohun tí kò dáa, yóò kú nítorí ìwà rẹ̀.+ 19 Àmọ́ tí ẹni burúkú bá yí pa dà kúrò nínú iṣẹ́ ibi rẹ̀, tó sì ń ṣe ohun tó tọ́ àti ohun tó jẹ́ òdodo, yóò máa wà láàyè torí ohun tó ṣe.+

20 “Àmọ́ ẹ ti sọ pé, ‘Ọ̀nà Jèhófà kò tọ́.’+ Èmi yóò fi ìwà kálukú dá a lẹ́jọ́, ìwọ ilé Ísírẹ́lì.”

21 Nígbà tó yá, ní ọjọ́ karùn-ún, oṣù kẹwàá, ọdún kejìlá tí a ti wà ní ìgbèkùn, ọkùnrin kan tó sá àsálà kúrò ní Jerúsálẹ́mù wá bá mi,+ ó sì sọ pé: “Wọ́n ti pa ìlú náà run!”+

22 Àmọ́ ní alẹ́ tó ṣáájú ọjọ́ tí ọkùnrin tó sá àsálà náà wá, ọwọ́ Jèhófà wá sára mi, ó sì ti la ẹnu mi kí ọkùnrin náà tó wá bá mi ní àárọ̀. Ẹnu mi wá là, mi ò sì yadi mọ́.+

23 Ni Jèhófà bá bá mi sọ̀rọ̀, ó ní: 24 “Ọmọ èèyàn, àwọn tó ń gbé ibi àwókù yìí+ ń sọ nípa ilẹ̀ Ísírẹ́lì pé, ‘Ẹnì kan péré ni Ábúráhámù, síbẹ̀ ó gba ilẹ̀ náà.+ Àmọ́ àwa pọ̀; ó dájú pé wọ́n ti fún wa ní ilẹ̀ náà kó lè di ohun ìní wa.’

25 “Torí náà, sọ fún wọn pé, ‘Ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí: “Ẹ̀ ń jẹ oúnjẹ tòun ti ẹ̀jẹ̀ rẹ̀,+ ẹ̀ ń gbé ojú yín sókè sí àwọn òrìṣà ẹ̀gbin* yín, ẹ sì ń ta ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀.+ Ẹ sì wá rò pé ilẹ̀ náà máa di tiyín? 26 Ẹ ti gbẹ́kẹ̀ lé idà yín,+ ẹ̀ ń ṣe ohun tó ń ríni lára, kálukú yín sì ti bá ìyàwó ọmọnìkejì rẹ̀ sùn.+ Ẹ sì wá rò pé ilẹ̀ náà máa di tiyín?”’+

27 “Ohun tí ìwọ yóò sọ fún wọn ni pé, ‘Ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí: “Bí mo ti wà láàyè, wọ́n á fi idà pa àwọn tó ń gbé inú àwókù náà; èmi yóò sọ àwọn tó wà lórí pápá gbalasa di oúnjẹ fún àwọn ẹranko; àrùn yóò sì pa àwọn tó wà nínú ibi ààbò àti ihò inú àwọn àpáta.+ 28 Èmi yóò mú kí ilẹ̀ náà di ahoro pátápátá,+ òpin á sì dé bá ìgbéraga rẹ̀, àwọn òkè Ísírẹ́lì yóò di ahoro,+ ẹnikẹ́ni ò sì ní gba ibẹ̀ kọjá. 29 Wọ́n á sì wá mọ̀ pé èmi ni Jèhófà, nígbà tí mo bá mú kí ilẹ̀ náà di ahoro pátápátá,+ nítorí gbogbo ohun ìríra tí wọ́n ṣe.”’+

30 “Ní tìrẹ, ọmọ èèyàn, àwọn èèyàn rẹ ń bá ara wọn sọ̀rọ̀ nípa rẹ lẹ́gbẹ̀ẹ́ àwọn ògiri àti ní ẹnu ọ̀nà àwọn ilé.+ Wọ́n ń sọ fún ara wọn, kálukú ń sọ fún arákùnrin rẹ̀ pé, ‘Ẹ wá, ẹ jẹ́ ká gbọ́ ọ̀rọ̀ Jèhófà.’ 31 Wọn yóò rọ́ wá bá ọ, kí wọ́n lè jókòó síwájú rẹ bí èèyàn mi; wọ́n á sì gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ, àmọ́ wọn ò ní ṣe ohun tí wọ́n gbọ́.+ Wọ́n ń fi ẹnu wọn sọ̀rọ̀ dídùn fún ọ,* àmọ́ bí wọ́n ṣe máa jèrè tí kò tọ́ ló wà lọ́kàn wọn. 32 Wò ó! Lójú wọn, o dà bí orin ìfẹ́, tí wọ́n fi ohùn dídùn kọ, tí wọ́n sì fi ohun ìkọrin olókùn tín-ín-rín kọ lọ́nà tó já fáfá. Wọ́n á gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ, àmọ́ wọn ò ní tẹ̀ lé e. 33 Ó máa ṣẹ, tó bá ti wá ṣẹ, wọ́n á wá mọ̀ pé wòlíì kan ti wà láàárín wọn.”+

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́