ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Jeremáyà 1
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Jeremáyà

      • Ọlọ́run yan Jeremáyà láti jẹ́ wòlíì (1-10)

      • Ìran nípa igi álímọ́ńdì (11, 12)

      • Ìran nípa ìkòkò ìsebẹ̀ (13-16)

      • Ọlọ́run fún Jeremáyà lágbára kó lè jẹ́ iṣẹ́ tó rán an (17-19)

Jeremáyà 1:1

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ó ṣeé ṣe kó túmọ̀ sí “Jèhófà Ń Gbéni Ga.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Joṣ 21:8, 18

Jeremáyà 1:2

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Ọb 22:1, 2
  • +2Ọb 21:19, 20

Jeremáyà 1:3

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Ọb 24:1; 2Kr 36:4
  • +2Ọb 24:18, 19
  • +2Ọb 25:8, 11; Jer 52:12, 15

Jeremáyà 1:5

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “yàn.”

  • *

    Ní Héb., “Kí o tó jáde láti inú ilé ọmọ.”

  • *

    Tàbí “yà ọ́ sọ́tọ̀.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ond 13:5; Sm 139:15, 16
  • +Lk 1:13, 15

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Jeremáyà, ojú ìwé 6-7

Jeremáyà 1:6

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ọ̀dọ́.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 4:10
  • +1Ọb 3:5, 7

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    3/15/2011, ojú ìwé 29

    Jeremáyà, ojú ìwé 7

Jeremáyà 1:7

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 7:1, 2

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Jeremáyà, ojú ìwé 191

Jeremáyà 1:8

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Isk 2:6
  • +Ẹk 3:11, 12; Jer 15:20; Iṣe 18:9, 10

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Jeremáyà, ojú ìwé 188-191

    Ilé Ìṣọ́,

    3/15/2007, ojú ìwé 9

    12/15/2005, ojú ìwé 24

Jeremáyà 1:9

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ais 6:7
  • +Ẹk 4:12, 15; Isk 33:7

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Jeremáyà, ojú ìwé 33-35

Jeremáyà 1:10

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jer 18:7-10; 24:5, 6

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    3/15/2011, ojú ìwé 30, 31-32

    Jeremáyà, ojú ìwé 168

Jeremáyà 1:11

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “ẹni tó ń tètè jí.”

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    3/15/2007, ojú ìwé 8-9

Jeremáyà 1:12

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    3/15/2011, ojú ìwé 28-29

    3/15/2007, ojú ìwé 8-9

    2/15/1993, ojú ìwé 32

Jeremáyà 1:13

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ìkòkò ìsebẹ̀ ẹlẹ́nu fífẹ̀.”

  • *

    Ní Héb., “tí wọ́n fẹ́ atẹ́gùn sí,” èyí tó fi hàn pé iná ń jó lala lábẹ́ rẹ̀.

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Jeremáyà, ojú ìwé 14-15

Jeremáyà 1:14

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jer 6:1; 10:22

Jeremáyà 1:15

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jer 5:15; 6:22; 25:9
  • +Jer 39:3
  • +Di 28:52; Jer 34:22; 44:6

Jeremáyà 1:16

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Joṣ 24:20; 2Ọb 22:17; 2Kr 7:19, 20
  • +Isk 8:10, 11; Ho 11:2
  • +Ais 2:8

Jeremáyà 1:17

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “de àmùrè mọ́ ìbàdí rẹ.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Isk 2:6

Jeremáyà 1:18

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jer 15:20; 20:11; Isk 3:8; Mik 3:8
  • +Jer 26:12

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    3/15/2011, ojú ìwé 32

Jeremáyà 1:19

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ṣẹ́gun.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 28:15; Ẹk 3:12; Joṣ 1:5

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Jeremáyà, ojú ìwé 88-89

    Ilé Ìṣọ́,

    4/1/2000, ojú ìwé 17

    3/2017, ojú ìwé 1

Àwọn míì

Jer. 1:1Joṣ 21:8, 18
Jer. 1:22Ọb 22:1, 2
Jer. 1:22Ọb 21:19, 20
Jer. 1:32Ọb 24:1; 2Kr 36:4
Jer. 1:32Ọb 24:18, 19
Jer. 1:32Ọb 25:8, 11; Jer 52:12, 15
Jer. 1:5Ond 13:5; Sm 139:15, 16
Jer. 1:5Lk 1:13, 15
Jer. 1:6Ẹk 4:10
Jer. 1:61Ọb 3:5, 7
Jer. 1:7Ẹk 7:1, 2
Jer. 1:8Isk 2:6
Jer. 1:8Ẹk 3:11, 12; Jer 15:20; Iṣe 18:9, 10
Jer. 1:9Ais 6:7
Jer. 1:9Ẹk 4:12, 15; Isk 33:7
Jer. 1:10Jer 18:7-10; 24:5, 6
Jer. 1:14Jer 6:1; 10:22
Jer. 1:15Jer 5:15; 6:22; 25:9
Jer. 1:15Jer 39:3
Jer. 1:15Di 28:52; Jer 34:22; 44:6
Jer. 1:16Joṣ 24:20; 2Ọb 22:17; 2Kr 7:19, 20
Jer. 1:16Isk 8:10, 11; Ho 11:2
Jer. 1:16Ais 2:8
Jer. 1:17Isk 2:6
Jer. 1:18Jer 15:20; 20:11; Isk 3:8; Mik 3:8
Jer. 1:18Jer 26:12
Jer. 1:19Jẹ 28:15; Ẹk 3:12; Joṣ 1:5
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
  • 1
  • 2
  • 3
  • 4
  • 5
  • 6
  • 7
  • 8
  • 9
  • 10
  • 11
  • 12
  • 13
  • 14
  • 15
  • 16
  • 17
  • 18
  • 19
Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
Jeremáyà 1:1-19

Jeremáyà

1 Ìwọ̀nyí ni ọ̀rọ̀ Jeremáyà,* ọmọ Hilikáyà, ọ̀kan lára àwọn àlùfáà tó wà ní Ánátótì,+ ní ilẹ̀ Bẹ́ńjámínì. 2 Jèhófà bá a sọ̀rọ̀ nígbà ayé Jòsáyà+ ọmọ Ámọ́nì,+ ọba Júdà, ní ọdún kẹtàlá tó ti ń jọba. 3 Ó tún bá a sọ̀rọ̀ nígbà ayé Jèhóákímù+ ọmọ Jòsáyà, ọba Júdà, títí di òpin ọdún kọkànlá ìjọba Sedekáyà,+ ọmọ Jòsáyà, ọba Júdà, títí Jerúsálẹ́mù fi lọ sí ìgbèkùn ní oṣù karùn-ún.+

4 Jèhófà bá mi sọ̀rọ̀, ó ní:

 5 “Kí n tó dá ọ nínú ìyá rẹ ni mo ti mọ̀* ọ́,+

Kí wọ́n sì tó bí ọ* ni mo ti sọ ọ́ di mímọ́.*+

Mo fi ọ́ ṣe wòlíì àwọn orílẹ̀-èdè.”

 6 Ṣùgbọ́n mo sọ pé: “Áà, Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ!

Mi ò mọ ọ̀rọ̀ sọ,+ ọmọdé* lásán ni mí.”+

 7 Ni Jèhófà bá sọ fún mi pé:

“Má sọ pé ‘ọmọdé lásán’ ni ọ́.

Torí o gbọ́dọ̀ lọ sọ́dọ̀ gbogbo àwọn tí mo bá rán ọ sí,

Kí o sì sọ gbogbo ohun tí mo bá pa láṣẹ fún ọ.+

 8 Má ṣe jẹ́ kí ìrísí wọn dẹ́rù bà ọ́,+

Nítorí ‘mo wà pẹ̀lú rẹ láti gbà ọ́,’+ ni Jèhófà wí.”

9 Jèhófà wá na ọwọ́ rẹ̀, ó sì fi kan ẹnu mi.+ Jèhófà sì sọ fún mi pé: “Mo ti fi ọ̀rọ̀ mi sí ẹnu rẹ.+ 10 Wò ó, mo ti fàṣẹ yàn ọ́ lónìí lórí àwọn orílẹ̀-èdè àti lórí àwọn ìjọba, láti fà tu àti láti bì wó, láti pa run àti láti ya lulẹ̀, láti kọ́ àti láti gbìn.”+

11 Jèhófà tún bá mi sọ̀rọ̀, ó ní: “Jeremáyà, kí lo rí?” Mo sọ pé: “Ẹ̀ka igi álímọ́ńdì.”*

12 Jèhófà sọ fún mi pé: “Òótọ́ ni, òun ni, nítorí mo máa ń wà lójúfò láti mú ọ̀rọ̀ mi ṣẹ.”

13 Jèhófà tún bá mi sọ̀rọ̀ lẹ́ẹ̀kejì pé: “Kí lo rí?” Torí náà, mo sọ pé: “Mo rí ìkòkò* tí ohun tó wà nínú rẹ̀ ń hó,* tí wọ́n da ẹnu rẹ̀ sẹ́gbẹ̀ẹ́ kí ó lè kọ ìdí sí àríwá.” 14 Ni Jèhófà bá sọ fún mi pé:

“Ìyọnu máa tú jáde láti àríwá

Sára gbogbo àwọn tó ń gbé ilẹ̀ náà.+

15 Nítorí ‘mò ń pe gbogbo ìdílé àwọn ìjọba àríwá,’ ni Jèhófà wí,+

‘Wọ́n á wá, kálukú wọn á sì ṣe ìtẹ́ rẹ̀

Sí àwọn ẹnubodè Jerúsálẹ́mù,+

Wọ́n á gbé e ti gbogbo ògiri tó yí i ká

Wọ́n á sì gbé e ti gbogbo ìlú tó wà ní Júdà.+

16 Màá kéde ìdájọ́ mi lé wọn lórí nítorí gbogbo ìwà ibi wọn,

Torí pé wọ́n ti fi mí sílẹ̀,+

Wọ́n ń fi ẹbọ rú èéfín sí àwọn ọlọ́run mìíràn+

Wọ́n sì ń forí balẹ̀ fún iṣẹ́ ọwọ́ ara wọn.’+

17 Àmọ́, gbára dì,*

Kí o sì dìde láti bá wọn sọ gbogbo ohun tí mo bá pa láṣẹ fún ọ.

Má ṣe jẹ́ kí ẹ̀rù wọn bà ọ́,+

Kí n má bàa jẹ́ kí ẹ̀rù bà ọ́ níwájú wọn.

18 Lónìí, mo ti sọ ọ́ di ìlú olódi,

Òpó irin àti ògiri bàbà láti kojú gbogbo ilẹ̀ náà,+

Láti kojú àwọn ọba Júdà àti àwọn ìjòyè rẹ̀,

Láti kojú àwọn àlùfáà rẹ̀ àti àwọn èèyàn ilẹ̀ náà.+

19 Ó sì dájú pé wọ́n á bá ọ jà,

Ṣùgbọ́n wọn kò ní borí* rẹ,

Nítorí ‘mo wà pẹ̀lú rẹ + láti gbà ọ́’ ni Jèhófà wí.”

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́