ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • nwt 2 Tímótì 1:1-4:22
  • 2 Tímótì

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • 2 Tímótì
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
2 Tímótì

ÌWÉ KEJÌ SÍ TÍMÓTÌ

1 Pọ́ọ̀lù, àpọ́sítélì Kristi Jésù nípasẹ̀ ìfẹ́ Ọlọ́run, èyí tó bá ìlérí ìyè tí a rí gbà nípasẹ̀ Kristi Jésù mu,+ 2 sí Tímótì, ọmọ tí mo nífẹ̀ẹ́:+

Kí o ní inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí, àánú àti àlàáfíà látọ̀dọ̀ Ọlọ́run tó jẹ́ Baba àti látọ̀dọ̀ Kristi Jésù Olúwa wa.

3 Mo dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run, ẹni tí mò ń fi ẹ̀rí ọkàn tó mọ́ ṣe iṣẹ́ ìsìn mímọ́ fún bí àwọn baba ńlá mi ti ṣe, mi ò sì yéé rántí rẹ nínú àwọn ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀ mi tọ̀sántòru. 4 Bí mo ṣe ń rántí omijé rẹ, àárò rẹ ń sọ mí, kí inú mi lè dùn gidigidi. 5 Torí mo rántí ìgbàgbọ́ rẹ tí kò ní ẹ̀tàn,+ èyí tí ìyá rẹ àgbà Lọ́ìsì àti ìyá rẹ Yùníìsì kọ́kọ́ ní, ó sì dá mi lójú pé irú ìgbàgbọ́ yìí ni ìwọ náà ní.

6 Torí èyí ni mo ṣe rán ọ létí pé kí o jẹ́ kí ẹ̀bùn Ọlọ́run tó wà nínú rẹ nígbà tí mo gbé ọwọ́ lé+ ọ máa jó bí iná. 7 Nítorí Ọlọ́run kò fún wa ní ẹ̀mí ojo,+ àmọ́ ó fún wa ní ẹ̀mí agbára+ àti ti ìfẹ́ àti ti àròjinlẹ̀. 8 Torí náà, má ṣe tijú láti jẹ́rìí nípa Olúwa wa+ tàbí èmi, ẹlẹ́wọ̀n nítorí rẹ̀, àmọ́ kí ìwọ náà jìyà torí ìhìn rere,+ kí o sì gbára lé agbára Ọlọ́run.+ 9 Ó gbà wá, ó sì fi ìpè mímọ́ pè wá,+ kì í ṣe torí àwọn iṣẹ́ wa, àmọ́ torí ohun tó fẹ́ ṣe àti inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí rẹ̀.+ Ọjọ́ pẹ́ tí a ti fún wa ní èyí nípasẹ̀ Kristi Jésù, 10 àmọ́ nísinsìnyí ìfarahàn Olùgbàlà wa, Kristi Jésù,+ ti mú kó ṣe kedere, ẹni tó mú ikú kúrò,+ tó sì tipasẹ̀ ìhìn rere+ tan ìmọ́lẹ̀ sí ìyè+ àti àìdíbàjẹ́.+ 11 Torí rẹ̀ ni a ṣe yàn mí láti di oníwàásù, àpọ́sítélì àti olùkọ́.+

12 Ìdí tí èmi náà ṣe ń jìyà àwọn nǹkan yìí nìyẹn,+ àmọ́ ojú ò tì mí.+ Torí mo mọ Ẹni tí mo gbà gbọ́, ó sì dá mi lójú pé ó lè dáàbò bo ohun tí mo fi sí ìkáwọ́ rẹ̀ títí di ọjọ́ náà.+ 13 Máa tẹ̀ lé ìlànà* àwọn ọ̀rọ̀ tó ṣàǹfààní*+ tí o gbọ́ lọ́dọ̀ mi pẹ̀lú ìgbàgbọ́ àti ìfẹ́ tó ń wá látinú àjọṣe tí a ní pẹ̀lú Kristi Jésù. 14 Máa fi ẹ̀mí mímọ́ tó ń gbé inú wa+ ṣọ́ ohun rere tí a fi síkàáwọ́ rẹ.

15 O mọ̀ pé gbogbo èèyàn ní ìpínlẹ̀ Éṣíà+ ti pa mí tì, títí kan Fíjẹ́lọ́sì àti Hẹmojẹ́nísì. 16 Kí Olúwa fi àánú hàn sí ìdílé Ónẹ́sífórù,+ torí pé ó máa ń mú kí ara tù mí lọ́pọ̀ ìgbà, kò sì tijú pé wọ́n fi ẹ̀wọ̀n dè mí. 17 Kàkà bẹ́ẹ̀, nígbà tó wà ní Róòmù, ó fara balẹ̀ wá mi, ó sì rí mi. 18 Kí Olúwa jẹ́ kó rí àánú gbà látọ̀dọ̀ Jèhófà* ní ọjọ́ yẹn. Gbogbo iṣẹ́ ìsìn tó ṣe ní Éfésù lo mọ̀ dáadáa.

2 Nítorí náà, ìwọ ọmọ mi,+ túbọ̀ máa gba agbára nípasẹ̀ inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí tó wà nínú Kristi Jésù; 2 àwọn nǹkan tí o sì gbọ́ lọ́dọ̀ mi, tí ọ̀pọ̀ èèyàn jẹ́rìí sí,+ àwọn nǹkan yìí ni kí o fi síkàáwọ́ àwọn olóòótọ́, tí àwọn náà á sì wá kúnjú ìwọ̀n dáadáa láti kọ́ àwọn ẹlòmíì. 3 Kí ìwọ náà múra tán láti jìyà+ nítorí ọmọ ogun rere+ fún Kristi Jésù ni ọ́. 4 Ọmọ ogun tó bá fẹ́ múnú ẹni tó gbà á sí iṣẹ́ ológun dùn, kò ní tara bọ* òwò* ṣíṣe. 5 Kódà nínú àwọn eré ìdíje, wọn kì í dé ẹni tó bá kópa ládé, àfi tó bá tẹ̀ lé àwọn òfin ìdíje náà.+ 6 Àgbẹ̀ tó ń ṣiṣẹ́ kára ló gbọ́dọ̀ kọ́kọ́ jẹ nínú àwọn èso oko. 7 Máa ronú nígbà gbogbo lórí àwọn ohun tí mò ń sọ; Olúwa máa fún ọ ní òye* nínú ohun gbogbo.

8 Rántí pé a jí Jésù Kristi dìde,+ ọmọ Dáfídì* sì ni,+ bó ṣe wà nínú ìhìn rere tí mò ń wàásù,+ 9 èyí tí mò ń torí rẹ̀ jìyà, tí wọ́n sì fi mí sẹ́wọ̀n bí ọ̀daràn.+ Àmọ́, ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ò ṣeé dè.+ 10 Nítorí èyí ni mo ṣe ń fara da ohun gbogbo torí àwọn àyànfẹ́,+ kí àwọn náà lè rí ìgbàlà tó wá nípasẹ̀ Kristi Jésù pẹ̀lú ògo àìnípẹ̀kun. 11 Ọ̀rọ̀ yìí ṣeé gbára lé: Ó dájú pé tí a bá jọ kú, a tún jọ máa wà láàyè;+ 12 tí a bá ń fara dà á nìṣó, a tún jọ máa jọba;+ tí a bá sẹ́ ẹ, òun náà máa sẹ́ wa;+ 13 tí a bá jẹ́ aláìṣòótọ́, ó ṣì máa jẹ́ olóòótọ́, torí kò lè sẹ́ ara rẹ̀.

14 Máa rán wọn létí àwọn nǹkan yìí, kí o máa fún wọn ní ìtọ́ni* níwájú Ọlọ́run pé kí wọ́n má ṣe jà nítorí ọ̀rọ̀, torí kò wúlò rárá, ó máa ń ṣàkóbá fún àwọn tó ń fetí sílẹ̀.* 15 Sa gbogbo ipá rẹ kí o lè rí ìtẹ́wọ́gbà Ọlọ́run, kí o jẹ́ òṣìṣẹ́ tí kò ní ohunkóhun tó máa tì í lójú, tó ń lo ọ̀rọ̀ òtítọ́ bó ṣe yẹ.+ 16 Àmọ́ yẹra fún àwọn ọ̀rọ̀ asán tó ń ba ohun mímọ́ jẹ́,+ torí ṣe ló máa ń mú kí èèyàn túbọ̀ jìnnà sí Ọlọ́run, 17 ọ̀rọ̀ wọn sì máa tàn kálẹ̀ bí egbò tó kẹ̀. Híméníọ́sì àti Fílétọ́sì wà lára wọn.+ 18 Àwọn ọkùnrin yìí ti yà kúrò nínú òtítọ́, wọ́n ń sọ pé àjíǹde ti ṣẹlẹ̀,+ wọ́n sì ń dojú ìgbàgbọ́ àwọn kan dé. 19 Síbẹ̀, ìpìlẹ̀ Ọlọ́run lágbára, ó dúró digbí, ó ní èdìdì yìí, “Jèhófà* mọ àwọn tó jẹ́ tirẹ̀,”+ àti pé, “Kí gbogbo àwọn tó ń pe orúkọ Jèhófà*+ kọ àìṣòdodo sílẹ̀ pátápátá.”

20 Àwọn ohun èlò wúrà àti fàdákà nìkan kọ́ ló wà nínú ilé ńlá, àmọ́ ohun èlò ti igi àti ti amọ̀ pẹ̀lú, wọ́n máa ń fi àwọn kan ṣe àwọn ohun tó ní ọlá, wọ́n sì ń fi àwọn míì ṣe ohun tí kò ní ọlá. 21 Torí náà, tí ẹnikẹ́ni bá yẹra fún àwọn tó kẹ́yìn yìí, wọ́n máa lò ó láti fi ṣe ohun tó ní ọlá,* tí a sọ di mímọ́, tó wúlò fún ẹni tó ni ín, tó sì múra tán láti ṣe gbogbo iṣẹ́ rere. 22 Torí náà, sá fún àwọn ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ìgbà ọ̀dọ́, àmọ́ máa wá òdodo, ìgbàgbọ́, ìfẹ́, àlàáfíà, pẹ̀lú àwọn tó ń fi ọkàn tó mọ́ ké pe Olúwa.

23 Bákan náà, má ṣe dá sí àwọn ìjiyàn tí kò bọ́gbọ́n mu àti ti àìmọ̀kan,+ o mọ̀ pé wọ́n máa ń fa ìjà. 24 Torí pé kò yẹ kí ẹrú Olúwa máa jà, àmọ́ ó yẹ kó máa hùwà jẹ́jẹ́* sí gbogbo èèyàn,+ kí ó kúnjú ìwọ̀n láti kọ́ni, kó máa kó ara rẹ̀ níjàánu tí wọ́n bá ṣe ohun tí kò dáa sí i,+ 25 kó máa fi ìwà tútù tọ́ àwọn tó ń ṣàtakò sọ́nà.+ Bóyá Ọlọ́run lè mú kí wọ́n ronú pìwà dà,* kí wọ́n sì wá ní ìmọ̀ tó péye nípa òtítọ́,+ 26 ká lè pe orí wọn wálé, kí wọ́n sì bọ́ lọ́wọ́ ìdẹkùn Èṣù, torí ó ti mú wọn láàyè kí wọ́n lè ṣe ìfẹ́ rẹ̀.+

3 Àmọ́ kí o mọ èyí pé, àwọn ọjọ́ ìkẹyìn+ yóò jẹ́ àkókò tí nǹkan máa le gan-an, tó sì máa nira. 2 Torí àwọn èèyàn máa nífẹ̀ẹ́ ara wọn nìkan, wọ́n á nífẹ̀ẹ́ owó, wọ́n á jẹ́ afọ́nnu, agbéraga, asọ̀rọ̀ òdì, aṣàìgbọràn sí òbí, aláìmoore, aláìṣòótọ́, 3 ẹni tí kò ní ìfẹ́ àdámọ́ni, kìígbọ́-kìígbà,* abanijẹ́, ẹni tí kò lè kó ara rẹ̀ níjàánu, ẹni tó burú gan-an, ẹni tí kò nífẹ̀ẹ́ ohun rere, 4 ọ̀dàlẹ̀, alágídí, ajọra-ẹni-lójú, wọ́n á fẹ́ràn ìgbádùn dípò Ọlọ́run, 5 wọ́n á jọ ẹni tó ń sin Ọlọ́run tọkàntọkàn, àmọ́ ìṣe wọn ò ní fi agbára rẹ̀ hàn;+ yẹra fún irú àwọn èèyàn bẹ́ẹ̀. 6 Lára wọn ni àwọn ọkùnrin kan ti jáde, tí wọ́n ń fi ẹ̀tàn wọnú àwọn agbo ilé, tí wọ́n sì ń tan àwọn aláìlera obìnrin tí ẹ̀ṣẹ̀ ti wọ̀ lọ́rùn, tí onírúurú ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ń darí, 7 gbogbo ìgbà ni wọ́n ń kẹ́kọ̀ọ́, síbẹ̀ wọn ò ní ìmọ̀ tó péye nípa òtítọ́ rárá.

8 Bí Jánésì àti Jáńbérì ṣe ta ko Mósè, bẹ́ẹ̀ náà ni àwọn yìí ṣe ń ta ko òtítọ́ ṣáá. Ìrònú irú àwọn èèyàn bẹ́ẹ̀ ti dìbàjẹ́, ìgbàgbọ́ wọn ò sì ní ìtẹ́wọ́gbà. 9 Síbẹ̀, wọn ò ní kọjá ibi tí wọ́n dé, torí ìwà òmùgọ̀* wọn máa hàn kedere sí gbogbo èèyàn, bíi tàwọn ọkùnrin méjì yẹn.+ 10 Àmọ́, o ti tẹ̀ lé ẹ̀kọ́ mi pẹ́kípẹ́kí, bí mo ṣe ń ṣe nǹkan,+ ohun tí mo ní lọ́kàn, ìgbàgbọ́ mi, sùúrù mi, ìfẹ́ mi, ìfaradà mi, 11 àwọn inúnibíni àti irú ìyà tó jẹ mí ní Áńtíókù,+ Íkóníónì+ àti Lísírà.+ Mo fara da àwọn inúnibíni yìí, Olúwa sì gbà mí nínú gbogbo wọn.+ 12 Ó dájú pé gbogbo àwọn tó bá fẹ́ fi ayé wọn sin Ọlọ́run tọkàntọkàn ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú Kristi Jésù ni wọ́n máa ṣe inúnibíni sí pẹ̀lú.+ 13 Àmọ́ àwọn èèyàn burúkú àti àwọn afàwọ̀rajà á máa burú sí i, wọ́n á máa ṣi àwọn èèyàn lọ́nà, wọ́n á sì máa ṣi àwọn náà lọ́nà.+

14 Àmọ́ kí ìwọ má ṣe fi àwọn nǹkan tí o ti kọ́ sílẹ̀, tí a sì mú kí o gbà gbọ́,*+ o sì mọ ọ̀dọ̀ àwọn tí o ti kọ́ wọn 15 àti pé láti kékeré jòjòló  + lo ti mọ ìwé mímọ́,+ èyí tó lè mú kí o di ọlọ́gbọ́n kí o lè rí ìgbàlà nípasẹ̀ ìgbàgbọ́ nínú Kristi Jésù.+ 16 Gbogbo Ìwé Mímọ́ ni Ọlọ́run mí sí,+ ó sì wúlò fún kíkọ́ni,+ fún bíbáni wí, fún mímú nǹkan tọ́,* fún títọ́nisọ́nà nínú òdodo,+ 17 kí èèyàn Ọlọ́run lè kúnjú ìwọ̀n dáadáa, kó sì lè gbára dì pátápátá fún gbogbo iṣẹ́ rere.

4 Mo pàṣẹ tó rinlẹ̀ yìí fún ọ níwájú Ọlọ́run àti Kristi Jésù, ẹni tó máa ṣèdájọ́+ àwọn alààyè àti òkú,+ nípasẹ̀ ìfarahàn rẹ̀+ àti Ìjọba rẹ̀:+ 2 Wàásù ọ̀rọ̀ náà;+ máa ṣe bẹ́ẹ̀ láìfi falẹ̀ ní àkókò tó rọrùn àti ní àkókò tí kò rọrùn; máa báni wí,+ máa fi ìbáwí tọ́ni sọ́nà, máa gbani níyànjú, pẹ̀lú ọ̀pọ̀ sùúrù àti ọ̀nà ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ tó dáa.*+ 3 Torí ìgbà kan ń bọ̀ tí wọn ò ní tẹ̀ lé ẹ̀kọ́ tó ṣàǹfààní,*+ àmọ́ wọ́n á máa ṣe ìfẹ́ inú ara wọn, wọ́n á fi àwọn olùkọ́ yí ara wọn ká, kí wọ́n lè máa sọ ohun tí wọ́n fẹ́ gbọ́.*+ 4 Wọn ò ní fetí sí òtítọ́ mọ́, ìtàn èké ni wọ́n á máa fetí sí. 5 Àmọ́, kí ìwọ máa ronú bó ṣe tọ́ nínú ohun gbogbo, fara da ìnira,+ ṣe iṣẹ́ ajíhìnrere,* ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ láìkù síbì kan.+

6 Torí ní báyìí, a ti ń tú mi jáde bí ọrẹ ohun mímu,+ a sì máa tó tú mi sílẹ̀.+ 7 Mo ti ja ìjà rere náà,+ mo ti sá eré ìje náà dé ìparí,+ mo ti pa ìgbàgbọ́ mọ́. 8 Láti ìsinsìnyí lọ, a ti fi adé òdodo  + pa mọ́ dè mí, èyí tí Olúwa, onídàájọ́ òdodo,+ máa fi san mí lẹ́san ní ọjọ́ yẹn,+ síbẹ̀ kì í ṣe fún èmi nìkan, àmọ́ fún gbogbo àwọn tó nífẹ̀ẹ́ ìfarahàn rẹ̀.

9 Sa gbogbo ipá rẹ láti wá sọ́dọ̀ mi láìpẹ́. 10 Ìdí ni pé Démà+ ti pa mí tì torí ó nífẹ̀ẹ́ ètò àwọn nǹkan yìí,* ó sì ti lọ sí Tẹsalóníkà, Kírẹ́sẹ́ńsì ti lọ sí Gálátíà, Títù sì ti lọ sí Damatíà. 11 Lúùkù nìkan ló wà lọ́dọ̀ mi. Mú Máàkù dání tí o bá ń bọ̀, torí ó ń ràn mí lọ́wọ́ lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́. 12 Àmọ́ mo ti rán Tíkíkù+ lọ sí Éfésù. 13 Tí o bá ń bọ̀, bá mi mú aṣọ àwọ̀lékè tí mo fi sílẹ̀ ní Tíróásì lọ́dọ̀ Kápọ́sì dání àti àwọn àkájọ ìwé, ní pàtàkì àwọn ìwé awọ.*

14 Alẹkisáńdà alágbẹ̀dẹ bàbà fi ojú mi rí màbo. Jèhófà* máa fi iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀ san án lẹ́san.+ 15 Kí ìwọ náà máa ṣọ́ra fún un, torí ó ń ta ko ọ̀rọ̀ wa gan-an.

16 Nígbà tí mo kọ́kọ́ lọ jẹ́jọ́, ẹnì kankan ò wá gbèjà mi, ṣe ni gbogbo wọn pa mí tì—kí a má ṣe kà á sí wọn lọ́rùn. 17 Àmọ́ Olúwa dúró tì mí, ó sì fún mi lágbára, ká lè lò mí láti ṣe iṣẹ́ ìwàásù láìkù síbì kan, kí gbogbo orílẹ̀-èdè lè gbọ́ ọ;+ ó sì gbà mí kúrò lẹ́nu kìnnìún.+ 18 Olúwa máa gbà mí lọ́wọ́ gbogbo iṣẹ́ burúkú, ó sì máa pa mí mọ́ kí n lè wọ ìjọba rẹ̀ ní ọ̀run.+ Òun ni kí ògo jẹ́ tirẹ̀ títí láé àti láéláé. Àmín.

19 Bá mi kí Pírísíkà àti Ákúílà+ àti agbo ilé Ónẹ́sífórù.+

20 Érásítù+ dúró sí Kọ́ríńtì, àmọ́ mo fi Tírófímù+ sílẹ̀ ní Mílétù, ara rẹ̀ ò yá. 21 Sa gbogbo ipá rẹ kí o lè dé kí ìgbà òtútù tó bẹ̀rẹ̀.

Yúbúlọ́sì ní kí n kí ọ, Púdéńsì àti Línúsì àti Kíláúdíà àti gbogbo àwọn ará pẹ̀lú ní kí n kí ọ.

22 Kí Olúwa wà pẹ̀lú ẹ̀mí tí o fi hàn. Kí inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí rẹ̀ wà pẹ̀lú rẹ.

Tàbí “àpẹẹrẹ.”

Tàbí “tó ṣeni lóore; tó wúlò.”

Wo Àfikún A5.

Ní Grk., “kó sínú.”

Tàbí kó jẹ́, “àwọn ìgbòkègbodò ojoojúmọ́.”

Tàbí “ìfòyemọ̀.”

Ní Grk., “èso Dáfídì.”

Ní Grk., “máa jẹ́rìí kúnnákúnná fún wọn.”

Tàbí “ń pa àwọn tó ń fetí sílẹ̀ run; ń dojú àwọn tó ń fetí sílẹ̀ dé.”

Wo Àfikún A5.

Wo Àfikún A5.

Tàbí “ó máa jẹ́ ohun èlò tó ní ọlá.”

Tàbí “fi ọgbọ́n hùwà.”

Tàbí “yí ọkàn pa dà.”

Tàbí “ẹni tí kì í fẹ́ ṣe àdéhùn.”

Tàbí “ìwà agọ̀.”

Ní Grk., “tí a sì ti yí ọ lérò pa dà láti gbà gbọ́.”

Tàbí “títún nǹkan ṣe.”

Ní Grk., “kí o sì máa lo ọnà ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́.”

Tàbí “tó ṣeni lóore; tó wúlò.”

Ní Grk., “kí wọ́n lè máa rin wọ́n ní etí.”

Tàbí “máa wàásù ìhìn rere náà.”

Tàbí “àsìkò yìí.” Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.

Ìyẹn, àwọn àkájọ ìwé tí wọ́n fi awọ ṣe.

Wo Àfikún A5.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́