ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Ẹ́kísódù 34
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Ẹ́kísódù

      • Ó gbẹ́ àwọn wàláà òkúta míì (1-4)

      • Mósè rí ògo Jèhófà (5-9)

      • Ọlọ́run tún àwọn ọ̀rọ̀ májẹ̀mú náà sọ (10-28)

      • Ìtànṣán ń jáde lára awọ ojú Mósè (29-35)

Ẹ́kísódù 34:1

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Di 10:1
  • +Di 9:10
  • +Ẹk 32:19; Di 9:17

Ẹ́kísódù 34:2

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 19:20; 24:12

Ẹ́kísódù 34:3

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 19:12, 13

Ẹ́kísódù 34:5

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “àwọsánmà.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Iṣe 7:38
  • +Ẹk 6:3; 33:19

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àwọn Ìtẹ̀jáde Tá A Tọ́ka sí Nínú Ìwé Ìpàdé, 10/2020, ojú ìwé 2

Ẹ́kísódù 34:6

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “olóore ọ̀fẹ́.”

  • *

    Tàbí “inú rere onífẹ̀ẹ́ rẹ̀.”

  • *

    Tàbí “ìṣòtítọ́.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Lk 6:36
  • +Ẹk 22:27; 2Kr 30:9; Ne 9:17; Sm 86:15; Joẹ 2:13
  • +Nọ 14:18; 2Pe 3:9
  • +Jer 31:3; Ida 3:22; Mik 7:18
  • +Sm 31:5; Ro 2:2

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́ (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́),

    11/2021, ojú ìwé 2-3

    Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!, ẹ̀kọ́ 7

    Ilé Ìṣọ́ (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́),

    9/2017, ojú ìwé 8

    Sún Mọ́ Jèhófà, ojú ìwé 276-278

    Ilé Ìṣọ́,

    5/1/2009, ojú ìwé 18

    5/15/2005, ojú ìwé 23-25

    1/15/2002, ojú ìwé 13-15, 17-18

    10/1/1998, ojú ìwé 8, 12-13

    Ìmọ̀, ojú ìwé 28-30

Ẹ́kísódù 34:7

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Da 9:4
  • +Sm 103:12; Ais 55:7; Ef 4:32; 1Jo 1:9
  • +Di 32:35; Joṣ 24:19; Ro 2:5; 2Pe 2:4; Jud 14, 15
  • +Ẹk 20:5; Di 30:19; 1Sa 15:2

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Sún Mọ́ Jèhófà, ojú ìwé 115-117

    Ilé Ìṣọ́,

    5/1/2009, ojú ìwé 18

    5/15/2005, ojú ìwé 23-25

    1/15/2002, ojú ìwé 13-15, 17-18

    Ìmọ̀, ojú ìwé 28-30

Ẹ́kísódù 34:9

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “ọlọ́rùn líle.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 33:14
  • +Ẹk 32:9; 33:3
  • +Nọ 14:19

Ẹ́kísódù 34:10

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “dá.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Sa 7:23; Sm 147:19, 20
  • +Ẹk 33:16; Di 10:21

Ẹ́kísódù 34:11

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 19:5, 6; Di 12:28
  • +Ẹk 3:8; 33:2; Di 7:1

Ẹ́kísódù 34:12

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Di 7:2
  • +Ẹk 23:32, 33

Ẹ́kísódù 34:13

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 23:24; Di 12:3

Ẹ́kísódù 34:14

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “torí orúkọ Jèhófà ní nínú.”

  • *

    Tàbí “kò fẹ́ kí o ní ọlọ́run míì.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 20:3; 1Kọ 10:14; 1Jo 5:21
  • +Joṣ 24:19

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ìjọsìn Mímọ́, ojú ìwé 164-165

    Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun, ojú ìwé 1719-1720

    Ilé Ìṣọ́,

    10/15/2002, ojú ìwé 28

    9/15/1995, ojú ìwé 8-9

Ẹ́kísódù 34:15

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Kọ 10:20
  • +Nọ 25:2; 2Kọ 6:14

Ẹ́kísódù 34:16

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹsr 9:2
  • +Di 7:4; 31:16; Ond 2:17; 8:33; 1Ọb 11:2; Ne 13:26; Sm 106:28

Ẹ́kísódù 34:17

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 32:8; Le 19:4

Ẹ́kísódù 34:18

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Wo Àfikún B15.

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Le 23:6
  • +Ẹk 23:15

Ẹ́kísódù 34:19

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “gbogbo àkọ́bí tó ṣí ilé ọmọ kọ̀ọ̀kan.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 13:2; Lk 2:23
  • +Ẹk 22:30

Ẹ́kísódù 34:20

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 13:15; Nọ 18:15, 16

Ẹ́kísódù 34:21

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “kí ẹ pa sábáàtì mọ́.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Di 5:12

Ẹ́kísódù 34:22

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “wíìtì.”

  • *

    Wọ́n tún máa ń pè é ní Àjọyọ̀ Àtíbàbà (Àgọ́ Ìjọsìn).

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 23:16; Le 23:34

Ẹ́kísódù 34:23

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “akọ.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Di 16:16

Ẹ́kísódù 34:24

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 34:11

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    9/1/1998, ojú ìwé 20

    “Ete aiyeraiye,” ojú ìwé 112

Ẹ́kísódù 34:25

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 23:18
  • +Ẹk 12:10; Nọ 9:12

Ẹ́kísódù 34:26

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Nọ 18:8, 12; Di 26:2; Owe 3:9
  • +Ẹk 23:19; Di 14:21

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    3/15/2004, ojú ìwé 27

Ẹ́kísódù 34:27

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 24:4; Di 31:9, 11
  • +Ẹk 24:8; Di 4:13

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Sún Mọ́ Jèhófà, ojú ìwé 179-181

    Ilé Ìṣọ́,

    6/15/2012, ojú ìwé 26

Ẹ́kísódù 34:28

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “Ọ̀rọ̀ Mẹ́wàá.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Di 9:18
  • +Ẹk 31:18; Di 10:2

Ẹ́kísódù 34:29

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 32:15

Ẹ́kísódù 34:30

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Kọ 3:7

Ẹ́kísódù 34:32

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 24:3; Di 1:3

Ẹ́kísódù 34:33

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Kọ 3:13

Ẹ́kísódù 34:34

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Kọ 3:16
  • +Di 27:10

Ẹ́kísódù 34:35

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “bá a.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Kọ 3:7, 13

Àwọn míì

Ẹ́kís. 34:1Di 10:1
Ẹ́kís. 34:1Di 9:10
Ẹ́kís. 34:1Ẹk 32:19; Di 9:17
Ẹ́kís. 34:2Ẹk 19:20; 24:12
Ẹ́kís. 34:3Ẹk 19:12, 13
Ẹ́kís. 34:5Iṣe 7:38
Ẹ́kís. 34:5Ẹk 6:3; 33:19
Ẹ́kís. 34:6Lk 6:36
Ẹ́kís. 34:6Ẹk 22:27; 2Kr 30:9; Ne 9:17; Sm 86:15; Joẹ 2:13
Ẹ́kís. 34:6Nọ 14:18; 2Pe 3:9
Ẹ́kís. 34:6Jer 31:3; Ida 3:22; Mik 7:18
Ẹ́kís. 34:6Sm 31:5; Ro 2:2
Ẹ́kís. 34:7Da 9:4
Ẹ́kís. 34:7Sm 103:12; Ais 55:7; Ef 4:32; 1Jo 1:9
Ẹ́kís. 34:7Di 32:35; Joṣ 24:19; Ro 2:5; 2Pe 2:4; Jud 14, 15
Ẹ́kís. 34:7Ẹk 20:5; Di 30:19; 1Sa 15:2
Ẹ́kís. 34:9Ẹk 33:14
Ẹ́kís. 34:9Ẹk 32:9; 33:3
Ẹ́kís. 34:9Nọ 14:19
Ẹ́kís. 34:102Sa 7:23; Sm 147:19, 20
Ẹ́kís. 34:10Ẹk 33:16; Di 10:21
Ẹ́kís. 34:11Ẹk 19:5, 6; Di 12:28
Ẹ́kís. 34:11Ẹk 3:8; 33:2; Di 7:1
Ẹ́kís. 34:12Di 7:2
Ẹ́kís. 34:12Ẹk 23:32, 33
Ẹ́kís. 34:13Ẹk 23:24; Di 12:3
Ẹ́kís. 34:14Ẹk 20:3; 1Kọ 10:14; 1Jo 5:21
Ẹ́kís. 34:14Joṣ 24:19
Ẹ́kís. 34:151Kọ 10:20
Ẹ́kís. 34:15Nọ 25:2; 2Kọ 6:14
Ẹ́kís. 34:16Ẹsr 9:2
Ẹ́kís. 34:16Di 7:4; 31:16; Ond 2:17; 8:33; 1Ọb 11:2; Ne 13:26; Sm 106:28
Ẹ́kís. 34:17Ẹk 32:8; Le 19:4
Ẹ́kís. 34:18Le 23:6
Ẹ́kís. 34:18Ẹk 23:15
Ẹ́kís. 34:19Ẹk 13:2; Lk 2:23
Ẹ́kís. 34:19Ẹk 22:30
Ẹ́kís. 34:20Ẹk 13:15; Nọ 18:15, 16
Ẹ́kís. 34:21Di 5:12
Ẹ́kís. 34:22Ẹk 23:16; Le 23:34
Ẹ́kís. 34:23Di 16:16
Ẹ́kís. 34:24Ẹk 34:11
Ẹ́kís. 34:25Ẹk 23:18
Ẹ́kís. 34:25Ẹk 12:10; Nọ 9:12
Ẹ́kís. 34:26Nọ 18:8, 12; Di 26:2; Owe 3:9
Ẹ́kís. 34:26Ẹk 23:19; Di 14:21
Ẹ́kís. 34:27Ẹk 24:4; Di 31:9, 11
Ẹ́kís. 34:27Ẹk 24:8; Di 4:13
Ẹ́kís. 34:28Di 9:18
Ẹ́kís. 34:28Ẹk 31:18; Di 10:2
Ẹ́kís. 34:29Ẹk 32:15
Ẹ́kís. 34:302Kọ 3:7
Ẹ́kís. 34:32Ẹk 24:3; Di 1:3
Ẹ́kís. 34:332Kọ 3:13
Ẹ́kís. 34:342Kọ 3:16
Ẹ́kís. 34:34Di 27:10
Ẹ́kís. 34:352Kọ 3:7, 13
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
  • 1
  • 2
  • 3
  • 4
  • 5
  • 6
  • 7
  • 8
  • 9
  • 10
  • 11
  • 12
  • 13
  • 14
  • 15
  • 16
  • 17
  • 18
  • 19
  • 20
  • 21
  • 22
  • 23
  • 24
  • 25
  • 26
  • 27
  • 28
  • 29
  • 30
  • 31
  • 32
  • 33
  • 34
  • 35
Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
Ẹ́kísódù 34:1-35

Ẹ́kísódù

34 Lẹ́yìn náà, Jèhófà sọ fún Mósè pé: “Kí ìwọ fúnra rẹ gbẹ́ wàláà òkúta méjì, irú ti àkọ́kọ́,+ màá sì kọ àwọn ọ̀rọ̀ tó wà lórí àwọn wàláà àkọ́kọ́+ tí o fọ́ túútúú+ sára rẹ̀. 2 Múra sílẹ̀ de àárọ̀, torí ìwọ yóò gun Òkè Sínáì lọ ní àárọ̀, kí o sì dúró síbẹ̀ lórí òkè náà níwájú mi.+ 3 Àmọ́ ẹnikẹ́ni ò gbọ́dọ̀ bá ọ lọ, ẹnikẹ́ni ò sì gbọ́dọ̀ sí níbikíbi lórí òkè náà. Àwọn agbo ẹran tàbí ọ̀wọ́ ẹran pàápàá ò gbọ́dọ̀ jẹko níwájú òkè yẹn.”+

4 Mósè wá gbẹ́ wàláà òkúta méjì, irú ti àkọ́kọ́, ó gbéra ní àárọ̀ kùtù lọ sí Òkè Sínáì, bí Jèhófà ṣe pàṣẹ fún un, ó sì gbé wàláà òkúta méjì náà dání. 5 Jèhófà sọ̀ kalẹ̀+ nínú ìkùukùu,* ó dúró sọ́dọ̀ rẹ̀ níbẹ̀, ó sì kéde orúkọ Jèhófà.+ 6 Jèhófà ń kọjá níwájú rẹ̀, ó sì ń kéde pé: “Jèhófà, Jèhófà, Ọlọ́run aláàánú,+ tó ń gba tẹni rò,*+ tí kì í tètè bínú,+ tí ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀*+ àti òtítọ́*+ rẹ̀ sì pọ̀ gidigidi, 7 tó ń fi ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ hàn sí ẹgbẹẹgbẹ̀rún,+ tó ń dárí àṣìṣe, ìṣìnà àti ẹ̀ṣẹ̀ jini,+ àmọ́ tí kò ní ṣàìfi ìyà jẹ ẹlẹ́ṣẹ̀,+ tó ń fi ìyà ẹ̀ṣẹ̀ àwọn bàbá jẹ àwọn ọmọ àtàwọn ọmọ ọmọ, dórí ìran kẹta àti dórí ìran kẹrin.”+

8 Mósè sáré tẹrí ba, ó sì wólẹ̀. 9 Ó sọ pé: “Jèhófà, tí mo bá ti rí ojúure rẹ, jọ̀ọ́ Jèhófà, máa bá wa lọ kí o sì wà láàárín wa,+ bó tiẹ̀ jẹ́ pé alágídí* ni wá,+ kí o dárí àṣìṣe àti ẹ̀ṣẹ̀ wa jì,+ kí o sì mú wa bí ohun ìní rẹ.” 10 Ó fèsì pé: “Èmi yóò dá májẹ̀mú kan: Níṣojú gbogbo èèyàn rẹ, èmi yóò ṣe àwọn ohun àgbàyanu tí wọn ò ṣe* rí ní gbogbo ayé tàbí láàárín gbogbo orílẹ̀-èdè,+ gbogbo àwọn tí ẹ̀ ń gbé láàárín wọn yóò rí iṣẹ́ Jèhófà, torí ohun àgbàyanu ni màá ṣe fún yín.+

11 “Ẹ fiyè sí ohun tí mò ń pa láṣẹ fún yín lónìí.+ Èmi yóò lé àwọn Ámórì kúrò níwájú yín àti àwọn ọmọ Kénáánì, àwọn ọmọ Hétì, àwọn Pérísì, àwọn Hífì àti àwọn ará Jébúsì.+ 12 Ẹ ṣọ́ra, kí ẹ má ṣe bá àwọn tó ń gbé ilẹ̀ tí ẹ̀ ń lọ dá májẹ̀mú,+ kó má bàa di ìdẹkùn fún yín.+ 13 Ṣùgbọ́n kí ẹ wó àwọn pẹpẹ wọn, kí ẹ sì fọ́ àwọn ọwọ̀n òrìṣà wọn túútúú, kí ẹ sì wó àwọn òpó òrìṣà* wọn lulẹ̀.+ 14 O ò gbọ́dọ̀ forí balẹ̀ fún ọlọ́run míì,+ torí Jèhófà máa ń fẹ́* kí a jọ́sìn òun nìkan.* Àní, ó jẹ́ Ọlọ́run tó fẹ́ kí a máa sin òun nìkan.+ 15 Ẹ ṣọ́ra, kí ẹ má ṣe bá àwọn tó ń gbé ilẹ̀ náà dá májẹ̀mú, torí tí wọ́n bá ń bá àwọn ọlọ́run wọn ṣèṣekúṣe, tí wọ́n sì ń rúbọ sí àwọn ọlọ́run wọn,+ ẹnì kan yóò pè ọ́ wá, wàá sì jẹ nínú ẹbọ rẹ̀.+ 16 Ó sì dájú pé ẹ máa mú lára àwọn ọmọbìnrin wọn fún àwọn ọmọkùnrin yín,+ àwọn ọmọbìnrin wọn máa bá àwọn ọlọ́run wọn ṣèṣekúṣe, wọ́n á sì mú kí àwọn ọmọkùnrin yín bá àwọn ọlọ́run wọn ṣèṣekúṣe.+

17 “O ò gbọ́dọ̀ fi irin rọ àwọn ọlọ́run.+

18 “Kí ẹ máa ṣe Àjọyọ̀ Búrẹ́dì Aláìwú.+ Ẹ jẹ búrẹ́dì aláìwú bí mo ṣe pa á láṣẹ fún yín; ọjọ́ méje ni kí ẹ fi ṣe é ní àkókò rẹ̀ nínú oṣù Ábíbù,*+ torí oṣù Ábíbù lẹ kúrò ní Íjíbítì.

19 “Tèmi ni gbogbo ọmọkùnrin tó jẹ́ àkọ́bí,*+ pẹ̀lú gbogbo ẹran ọ̀sìn yín, yálà ó jẹ́ àkọ́bí akọ màlúù tàbí ti àgùntàn.+ 20 Kí ẹ fi àgùntàn ra àkọ́bí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ pa dà. Àmọ́ tí ẹ ò bá rà á pa dà, kí ẹ ṣẹ́ ọrùn rẹ̀. Kí ẹ ra gbogbo àkọ́bí nínú àwọn ọmọkùnrin yín pa dà.+ Ẹnikẹ́ni ò gbọ́dọ̀ wá síwájú mi lọ́wọ́ òfo.

21 “Ọjọ́ mẹ́fà ni kí ẹ fi ṣiṣẹ́, àmọ́ kí ẹ sinmi* ní ọjọ́ keje.+ Kódà, nígbà ìtúlẹ̀ àti ìkórè, kí ẹ sinmi.

22 “Kí ẹ fi àwọn èso yín tó kọ́kọ́ pọ́n nígbà ìkórè àlìkámà* ṣe Àjọyọ̀ Àwọn Ọ̀sẹ̀ àti Àjọyọ̀ Ìkórèwọlé* nígbà tí ọdún bá yí po.+

23 “Ẹ̀ẹ̀mẹta lọ́dún ni kí gbogbo ọkùnrin* yín wá síwájú Jèhófà, Olúwa tòótọ́, Ọlọ́run Ísírẹ́lì.+ 24 Torí màá lé àwọn orílẹ̀-èdè kúrò níwájú yín,+ màá sì mú kí ilẹ̀ yín fẹ̀, ilẹ̀ yín ò sì ní wọ ẹnikẹ́ni lójú nígbà tí ẹ bá ń gòkè lọ rí ojú Jèhófà Ọlọ́run yín lẹ́ẹ̀mẹta lọ́dún.

25 “O ò gbọ́dọ̀ fi ẹ̀jẹ̀ rúbọ sí mi pa pọ̀ pẹ̀lú ohun tó ní ìwúkàrà.+ Ẹbọ àjọyọ̀ Ìrékọjá ò gbọ́dọ̀ ṣẹ́ kù di àárọ̀.+

26 “Kí o mú èyí tó dáa jù nínú àwọn èso tó kọ́kọ́ pọ́n ní ilẹ̀ rẹ wá sí ilé Jèhófà Ọlọ́run rẹ.+

“O ò gbọ́dọ̀ se ọmọ ewúrẹ́ nínú wàrà ìyá rẹ̀.”+

27 Jèhófà wá sọ fún Mósè pé: “Kọ àwọn ọ̀rọ̀ yìí sílẹ̀,+ torí ọ̀rọ̀ wọ̀nyí ni èmi yóò fi bá ìwọ àti Ísírẹ́lì dá májẹ̀mú.”+ 28 Ó sì wà níbẹ̀ pẹ̀lú Jèhófà fún ogójì (40) ọ̀sán àti ogójì (40) òru. Kò jẹun rárá, kò sì mu omi.+ Ó sì kọ ọ̀rọ̀ májẹ̀mú náà sára àwọn wàláà náà, Òfin Mẹ́wàá.*+

29 Mósè wá sọ̀ kalẹ̀ látorí Òkè Sínáì, àwọn wàláà Ẹ̀rí méjì náà sì wà lọ́wọ́ rẹ̀.+ Nígbà tó sọ̀ kalẹ̀ látorí òkè náà, Mósè ò mọ̀ pé ìtànṣán ń jáde lára awọ ojú òun torí ó ti ń bá Ọlọ́run sọ̀rọ̀. 30 Nígbà tí Áárónì àti gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì rí Mósè, wọ́n rí i pé ìtànṣán ń jáde lára awọ ojú rẹ̀, ẹ̀rù sì ń bà wọ́n láti sún mọ́ ọn.+

31 Àmọ́ Mósè pè wọ́n, Áárónì àti gbogbo ìjòyè àpéjọ náà sì wá sọ́dọ̀ rẹ̀, Mósè sì bá wọn sọ̀rọ̀. 32 Lẹ́yìn ìyẹn, gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sún mọ́ ọn, ó sì sọ gbogbo àṣẹ tí Jèhófà pa fún un lórí Òkè Sínáì fún wọn.+ 33 Tí Mósè bá ti bá wọn sọ̀rọ̀ tán, á fi nǹkan bojú.+ 34 Àmọ́ tí Mósè bá fẹ́ wọlé lọ bá Jèhófà sọ̀rọ̀, á ṣí ìbòjú náà kúrò títí á fi jáde.+ Ó wá jáde, ó sì sọ àwọn àṣẹ tó gbà fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.+ 35 Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì rí i pé ìtànṣán ń jáde lára awọ ojú Mósè; torí náà, Mósè lo ìbòjú náà títí ó fi wọlé lọ bá Ọlọ́run* sọ̀rọ̀.+

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́