ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Nọ́ńbà 24
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Nọ́ńbà

      • Báláámù sọ̀rọ̀ lówelówe nígbà kẹta (1-11)

      • Báláámù sọ̀rọ̀ lówelówe nígbà kẹrin (12-25)

Nọ́ńbà 24:1

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “ó dáa ní ojú Jèhófà.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Nọ 23:3, 15, 23

Nọ́ńbà 24:2

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Nọ 2:2; 23:9
  • +1Sa 19:20

Nọ́ńbà 24:3

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Nọ 23:7, 18

Nọ́ńbà 24:4

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Nọ 24:16

Nọ́ńbà 24:5

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Nọ 1:52; 2:2

Nọ́ńbà 24:6

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Nọ 22:11

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    2/1/2014, ojú ìwé 10

Nọ́ńbà 24:7

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “àtọmọdọ́mọ.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Di 8:7
  • +Jẹ 49:10; Sm 2:6; Jo 1:49
  • +Nọ 24:20
  • +1Kr 14:2; Da 2:44; Ifi 11:15

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé-Ìṣọ́nà,

    7/15/1992, ojú ìwé 5

Nọ́ńbà 24:8

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 23:27; Di 9:5

Nọ́ńbà 24:9

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 12:1-3; 27:29

Nọ́ńbà 24:10

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Nọ 22:10, 11; 23:11; Ne 13:1, 2

Nọ́ńbà 24:11

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Nọ 22:16, 17

Nọ́ńbà 24:13

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “tó wà lọ́kàn mi.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Nọ 22:18, 38

Nọ́ńbà 24:14

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ní òpin àwọn ọjọ́.”

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àwọn Ìtẹ̀jáde Tá A Tọ́ka sí Nínú Ìwé Ìpàdé, 5/2022,

Nọ́ńbà 24:15

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Nọ 23:7
  • +Nọ 24:3, 4

Nọ́ńbà 24:17

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ẹ̀bátí orí Móábù.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ifi 22:16
  • +Sm 110:2; Heb 1:8
  • +2Sa 7:16, 17; Ais 9:7
  • +2Sa 8:2; 1Kr 18:2; Sm 108:9

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ìparí Ìṣípayá, ojú ìwé 53, 318

    Ilé Ìṣọ́,

    5/15/2005, ojú ìwé 17

Nọ́ńbà 24:18

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 27:37; 2Sa 8:14; Emọ 9:11, 12
  • +Jẹ 36:8; Joṣ 24:4
  • +1Kr 4:42, 43; Isk 25:14

Nọ́ńbà 24:19

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 49:10; Sm 2:9; 72:11; Ifi 6:2; 19:15

Nọ́ńbà 24:20

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 17:8, 14
  • +Di 25:19; 1Sa 15:3; 1Kr 4:43

Nọ́ńbà 24:21

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 15:18, 19; Ond 1:16

Nọ́ńbà 24:24

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 10:2, 4; Isk 27:6
  • +Na 3:18

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    10/15/2007, ojú ìwé 18-19

Nọ́ńbà 24:25

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Nọ 31:7, 8

Àwọn míì

Nọ́ń. 24:1Nọ 23:3, 15, 23
Nọ́ń. 24:2Nọ 2:2; 23:9
Nọ́ń. 24:21Sa 19:20
Nọ́ń. 24:3Nọ 23:7, 18
Nọ́ń. 24:4Nọ 24:16
Nọ́ń. 24:5Nọ 1:52; 2:2
Nọ́ń. 24:6Nọ 22:11
Nọ́ń. 24:7Di 8:7
Nọ́ń. 24:7Jẹ 49:10; Sm 2:6; Jo 1:49
Nọ́ń. 24:7Nọ 24:20
Nọ́ń. 24:71Kr 14:2; Da 2:44; Ifi 11:15
Nọ́ń. 24:8Ẹk 23:27; Di 9:5
Nọ́ń. 24:9Jẹ 12:1-3; 27:29
Nọ́ń. 24:10Nọ 22:10, 11; 23:11; Ne 13:1, 2
Nọ́ń. 24:11Nọ 22:16, 17
Nọ́ń. 24:13Nọ 22:18, 38
Nọ́ń. 24:15Nọ 23:7
Nọ́ń. 24:15Nọ 24:3, 4
Nọ́ń. 24:17Ifi 22:16
Nọ́ń. 24:17Sm 110:2; Heb 1:8
Nọ́ń. 24:172Sa 7:16, 17; Ais 9:7
Nọ́ń. 24:172Sa 8:2; 1Kr 18:2; Sm 108:9
Nọ́ń. 24:18Jẹ 27:37; 2Sa 8:14; Emọ 9:11, 12
Nọ́ń. 24:18Jẹ 36:8; Joṣ 24:4
Nọ́ń. 24:181Kr 4:42, 43; Isk 25:14
Nọ́ń. 24:19Jẹ 49:10; Sm 2:9; 72:11; Ifi 6:2; 19:15
Nọ́ń. 24:20Ẹk 17:8, 14
Nọ́ń. 24:20Di 25:19; 1Sa 15:3; 1Kr 4:43
Nọ́ń. 24:21Jẹ 15:18, 19; Ond 1:16
Nọ́ń. 24:24Jẹ 10:2, 4; Isk 27:6
Nọ́ń. 24:24Na 3:18
Nọ́ń. 24:25Nọ 31:7, 8
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
  • 1
  • 2
  • 3
  • 4
  • 5
  • 6
  • 7
  • 8
  • 9
  • 10
  • 11
  • 12
  • 13
  • 14
  • 15
  • 16
  • 17
  • 18
  • 19
  • 20
  • 21
  • 22
  • 23
  • 24
  • 25
Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
Nọ́ńbà 24:1-25

Nọ́ńbà

24 Nígbà tí Báláámù wá rí i pé ó wu Jèhófà* láti súre fún Ísírẹ́lì, kò tún lọ wá bó ṣe máa ríran ìparun+ mọ́, àmọ́ ó yíjú sí aginjù. 2 Nígbà tí Báláámù wòkè tó sì rí i tí Ísírẹ́lì pàgọ́ wọn ní ẹ̀yà-ẹ̀yà,+ ẹ̀mí Ọlọ́run wá bà lé e.+ 3 Ó sì sọ̀rọ̀ lówelówe pé: +

“Ọ̀rọ̀ Báláámù ọmọ Béórì,

Àti ọ̀rọ̀ ẹnu ọkùnrin tí ojú rẹ̀ ti là,

 4 Ọ̀rọ̀ ẹni tó ń gbọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run,

Tó rí ìran Olódùmarè,

Tó wólẹ̀ nígbà tí ojú rẹ̀ là:+

 5 Àwọn àgọ́ rẹ mà rẹwà o, ìwọ Jékọ́bù,

Àwọn ibùgbé rẹ, ìwọ Ísírẹ́lì!+

 6 Wọ́n tẹ́ lọ rẹrẹ+ bí àwọn àfonífojì,

Bí àwọn ọgbà tó wà létí odò,

Bí àwọn ewéko álóè tí Jèhófà gbìn,

Bí àwọn igi kédárì létí omi.

 7 Omi ń sun látinú àwọn korobá rẹ̀ méjì tí wọ́n fi awọ ṣe,

Etí omi+ ló sì gbin àwọn irúgbìn* rẹ̀ sí.

Ọba+ rẹ̀ pẹ̀lú yóò ju Ágágì+ lọ,

Wọ́n á sì gbé ìjọba rẹ̀ ga.+

 8 Ọlọ́run ń mú un kúrò ní Íjíbítì.

Ó dà bí ìwo akọ màlúù igbó fún wọn.

Ó máa jẹ àwọn orílẹ̀-èdè run, àwọn tó ń ni ín lára,+

Ó máa jẹ egungun wọn run, ó sì máa fi àwọn ọfà rẹ̀ run wọ́n.

 9 Ó ti dùbúlẹ̀, ó sùn sílẹ̀ bíi kìnnìún,

Bíi kìnnìún, ta ló láyà láti jí i?

Ìbùkún ni fún àwọn tó ń súre fún ọ,

Ègún sì ni fún àwọn tó ń gégùn-ún+ fún ọ.”

10 Inú wá bí Bálákì sí Báláámù gan-an. Bálákì wá fi ìbínú pàtẹ́wọ́, ó sì sọ fún Báláámù pé: “Torí kí o lè gégùn-ún fún àwọn ọ̀tá mi ni mo ṣe pè ọ́ + wá, àmọ́ ṣe lo kàn ń súre fún wọn lẹ́ẹ̀mẹta yìí. 11 Ó yá, tètè pa dà sílé. Mo fẹ́ dá ọ lọ́lá gan-an+ tẹ́lẹ̀ ni, àmọ́ wò ó! Jèhófà ò jẹ́ kí n dá ọ lọ́lá.”

12 Báláámù dá Bálákì lóhùn pé: “Ṣebí mo sọ fún àwọn tí o rán pé, 13 ‘Bí Bálákì bá tiẹ̀ fún mi ní ilé rẹ̀ tí fàdákà àti wúrà kún inú rẹ̀, mi ò kàn ní ṣe ohunkóhun tó wù mí,* tó lòdì sí àṣẹ Jèhófà, bóyá ó dáa tàbí kò dáa. Ọ̀rọ̀ tí Jèhófà bá sọ fún mi nìkan ni màá sọ’?+ 14 Ní báyìí, mo fẹ́ pa dà sọ́dọ̀ àwọn èèyàn mi. Wá, jẹ́ kí n sọ fún ọ, ohun tí àwọn èèyàn yìí máa ṣe fún àwọn èèyàn rẹ lọ́jọ́ iwájú.”* 15 Ó wá sọ̀rọ̀ lówelówe pé:+

“Ọ̀rọ̀ Báláámù ọmọ Béórì,

Àti ọ̀rọ̀ ẹnu ọkùnrin tí ojú rẹ̀ ti là,+

16 Ọ̀rọ̀ ẹni tó ń gbọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run,

Àti ẹni tó ní ìmọ̀ Ẹni Gíga Jù Lọ,

Ó rí ìran Olódùmarè

Nígbà tó wólẹ̀, tí ojú rẹ̀ là:

17 Màá rí i, àmọ́ kì í ṣe báyìí;

Màá wò ó, àmọ́ kò tíì yá.

Ìràwọ̀ kan+ máa ti ọ̀dọ̀ Jékọ́bù wá,

Ọ̀pá àṣẹ+ kan sì máa dìde láti Ísírẹ́lì.+

Ó sì dájú pé ó máa fọ́ iwájú orí Móábù*+ sí wẹ́wẹ́

Àti agbárí gbogbo àwọn ọmọ ìdàrúdàpọ̀.

18 Édómù sì máa di ohun ìní,+

Àní, Séírì+ máa di ohun ìní àwọn ọ̀tá+ rẹ̀,

Bí Ísírẹ́lì ṣe ń fi hàn pé òun nígboyà.

19 Ẹnì kan yóò ti ọ̀dọ̀ Jékọ́bù wá, tí yóò máa ṣẹ́gun lọ,+

Yóò sì pa ẹnikẹ́ni tó bá yè bọ́ nínú ìlú náà run.”

20 Nígbà tó rí Ámálékì, ó ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ lówelówe pé:

“Ámálékì ni àkọ́kọ́ nínú àwọn orílẹ̀-èdè,+

Àmọ́ ṣe ló máa ṣègbé+ nígbẹ̀yìn-gbẹ́yín.”

21 Nígbà tó rí àwọn Kénì,+ ó ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ lówelówe pé:

“Ibùgbé rẹ ní ààbò, orí àpáta sì ni ilé rẹ fìkàlẹ̀ sí.

22 Àmọ́ ẹnì kan máa sun Kénì kanlẹ̀.

Ìgbà mélòó ló kù tí Ásíríà fi máa kó ọ lẹ́rú?”

23 Ó ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ lówelówe pé:

“Ó mà ṣe o! Ta ló máa yè bọ́ tí Ọlọ́run bá ṣe èyí?

24 Àwọn ọkọ̀ òkun máa wá láti etíkun Kítímù,+

Wọ́n á sì fìyà jẹ Ásíríà,+

Wọ́n á tún fìyà jẹ Ébérì.

Àmọ́ ṣe lòun náà máa ṣègbé pátápátá.”

25 Báláámù+ wá dìde, ó sì lọ, ó pa dà síbi tó ti wá. Bálákì náà sì bá ọ̀nà tirẹ̀ lọ.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́