ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Àìsáyà 51
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Àìsáyà

      • Síónì máa pa dà rí bí ọgbà Édẹ́nì (1-8)

      • Aṣẹ̀dá Síónì tó lágbára tù wọ́n nínú (9-16)

      • Ife ìbínú Jèhófà (17-23)

Àìsáyà 51:1

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kejì, ojú ìwé 165-166, 167-168

Àìsáyà 51:2

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “bí yín pẹ̀lú ìrora ìbímọ.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 21:2
  • +Jẹ 12:1; 15:2
  • +1Ọb 4:20

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kejì, ojú ìwé 166-168

Àìsáyà 51:3

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Sm 102:13; Ais 66:13; Jer 31:12
  • +Ais 44:26; 61:4
  • +Jẹ 2:8
  • +Ais 35:1; 41:18
  • +Jer 33:10, 11

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kejì, ojú ìwé 168-169

Àìsáyà 51:4

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 19:6; Di 7:6
  • +Ais 2:3; Mik 4:2
  • +Owe 6:23

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kejì, ojú ìwé 169

Àìsáyà 51:5

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “agbára.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ais 46:13
  • +Ais 12:2; 56:1
  • +1Sa 2:10; Ais 2:4
  • +Ais 60:9

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kejì, ojú ìwé 169-170

Àìsáyà 51:6

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ò sì ní fọ́ túútúú.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ais 45:17
  • +Sm 102:25-27; Mt 24:35

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kejì, ojú ìwé 170-171

Àìsáyà 51:7

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ìtọ́ni.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jer 31:33

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kejì, ojú ìwé 171-172

Àìsáyà 51:8

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “kòkòrò.”

  • *

    Tàbí kó jẹ́, “Kòkòrò mùkúlú.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ais 50:9
  • +Ais 45:17; Lk 1:50

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kejì, ojú ìwé 171-172

Àìsáyà 51:9

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Lk 1:51
  • +Sm 87:4; 89:10; Ais 30:7
  • +Ẹk 15:4; Ne 9:10, 11; Sm 106:22; Isk 29:3

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kejì, ojú ìwé 172-173

Àìsáyà 51:10

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 14:21, 22
  • +Sm 106:9

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kejì, ojú ìwé 172-173

Àìsáyà 51:11

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “wà lórí wọn.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jer 31:11; Sek 10:10
  • +Ais 35:10
  • +Ais 61:7
  • +Ais 25:8; 65:18, 19

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ìparí Ìṣípayá, ojú ìwé 303

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kejì, ojú ìwé 173-174

Àìsáyà 51:12

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ais 49:13; 66:13
  • +Sm 118:6; Da 3:16, 17; Mt 10:28

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kejì, ojú ìwé 174

Àìsáyà 51:13

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ẹni tó sé ọ mọ́.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ais 44:2
  • +Ais 40:22

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    5/15/2005, ojú ìwé 32

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kejì, ojú ìwé 174

Àìsáyà 51:14

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹsr 1:2, 3; Ais 48:20; 52:2

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kejì, ojú ìwé 174-175

Àìsáyà 51:15

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jer 31:35, 36; Jon 1:4
  • +Ais 47:4

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kejì, ojú ìwé 175

Àìsáyà 51:16

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Di 33:27; Sm 91:1
  • +Ais 65:17; 66:8, 22
  • +Ais 60:14; Jer 31:33; Sek 8:8

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kejì, ojú ìwé 175-176

Àìsáyà 51:17

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ais 52:1; 60:1
  • +Jer 25:15

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kejì, ojú ìwé 176

Àìsáyà 51:18

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kejì, ojú ìwé 176-177

Àìsáyà 51:19

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Isk 14:21
  • +Ida 1:17

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kejì, ojú ìwé 176-179

Àìsáyà 51:20

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “ìkóríta.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ida 2:11

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kejì, ojú ìwé 176-179

Àìsáyà 51:22

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ais 51:17
  • +Ais 54:9; 62:8

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kejì, ojú ìwé 179

Àìsáyà 51:23

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ọkàn rẹ.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ais 49:25

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kejì, ojú ìwé 179

Àwọn míì

Àìsá. 51:2Jẹ 21:2
Àìsá. 51:2Jẹ 12:1; 15:2
Àìsá. 51:21Ọb 4:20
Àìsá. 51:3Sm 102:13; Ais 66:13; Jer 31:12
Àìsá. 51:3Ais 44:26; 61:4
Àìsá. 51:3Jẹ 2:8
Àìsá. 51:3Ais 35:1; 41:18
Àìsá. 51:3Jer 33:10, 11
Àìsá. 51:4Ẹk 19:6; Di 7:6
Àìsá. 51:4Ais 2:3; Mik 4:2
Àìsá. 51:4Owe 6:23
Àìsá. 51:5Ais 46:13
Àìsá. 51:5Ais 12:2; 56:1
Àìsá. 51:51Sa 2:10; Ais 2:4
Àìsá. 51:5Ais 60:9
Àìsá. 51:6Ais 45:17
Àìsá. 51:6Sm 102:25-27; Mt 24:35
Àìsá. 51:7Jer 31:33
Àìsá. 51:8Ais 50:9
Àìsá. 51:8Ais 45:17; Lk 1:50
Àìsá. 51:9Lk 1:51
Àìsá. 51:9Sm 87:4; 89:10; Ais 30:7
Àìsá. 51:9Ẹk 15:4; Ne 9:10, 11; Sm 106:22; Isk 29:3
Àìsá. 51:10Ẹk 14:21, 22
Àìsá. 51:10Sm 106:9
Àìsá. 51:11Jer 31:11; Sek 10:10
Àìsá. 51:11Ais 35:10
Àìsá. 51:11Ais 61:7
Àìsá. 51:11Ais 25:8; 65:18, 19
Àìsá. 51:12Ais 49:13; 66:13
Àìsá. 51:12Sm 118:6; Da 3:16, 17; Mt 10:28
Àìsá. 51:13Ais 44:2
Àìsá. 51:13Ais 40:22
Àìsá. 51:14Ẹsr 1:2, 3; Ais 48:20; 52:2
Àìsá. 51:15Jer 31:35, 36; Jon 1:4
Àìsá. 51:15Ais 47:4
Àìsá. 51:16Di 33:27; Sm 91:1
Àìsá. 51:16Ais 65:17; 66:8, 22
Àìsá. 51:16Ais 60:14; Jer 31:33; Sek 8:8
Àìsá. 51:17Ais 52:1; 60:1
Àìsá. 51:17Jer 25:15
Àìsá. 51:19Isk 14:21
Àìsá. 51:19Ida 1:17
Àìsá. 51:20Ida 2:11
Àìsá. 51:22Ais 51:17
Àìsá. 51:22Ais 54:9; 62:8
Àìsá. 51:23Ais 49:25
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
  • 1
  • 2
  • 3
  • 4
  • 5
  • 6
  • 7
  • 8
  • 9
  • 10
  • 11
  • 12
  • 13
  • 14
  • 15
  • 16
  • 17
  • 18
  • 19
  • 20
  • 21
  • 22
  • 23
Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
Àìsáyà 51:1-23

Àìsáyà

51 “Ẹ fetí sí mi, ẹ̀yin tí ẹ̀ ń lépa òdodo,

Ẹ̀yin tí ẹ̀ ń wá Jèhófà.

Ẹ yíjú sí àpáta tí a ti gbẹ́ yín jáde

Àti ibi tí wọ́n ti ń wa òkúta, tí a ti wà yín jáde.

 2 Ẹ yíjú sí Ábúráhámù bàbá yín

Àti Sérà+ tó bí yín.*

Torí ọ̀kan ṣoṣo ni nígbà tí mo pè é,+

Mo wá bù kún un, mo sì sọ ọ́ di púpọ̀.+

 3 Torí Jèhófà máa tu Síónì nínú.+

Ó máa tu gbogbo àwókù rẹ̀ nínú,+

Ó máa mú kí aginjù rẹ̀ rí bí Édẹ́nì,+

Ó sì máa mú kí aṣálẹ̀ rẹ̀ tó tẹ́jú rí bí ọgbà Jèhófà.+

Ìdùnnú àti ayọ̀ máa wà níbẹ̀,

Ìdúpẹ́ àti orin tó dùn.+

 4 Ẹ gbọ́ mi, ẹ̀yin èèyàn mi,

Kí o sì fetí sí mi, orílẹ̀-èdè mi.+

Torí òfin kan máa jáde látọ̀dọ̀ mi,+

Màá sì mú kí ìdájọ́ òdodo mi fìdí múlẹ̀ bí ìmọ́lẹ̀ fún àwọn èèyàn.+

 5 Òdodo mi sún mọ́lé.+

Ìgbàlà mi máa jáde lọ,+

Apá mi sì máa dá àwọn èèyàn lẹ́jọ́.+

Àwọn erékùṣù máa nírètí nínú mi,+

Wọ́n sì máa dúró de apá* mi.

 6 Ẹ gbé ojú yín sókè sí ọ̀run,

Kí ẹ sì wo ayé nísàlẹ̀.

Torí pé ọ̀run máa fẹ́ lọ bí èéfín;

Ayé máa gbó bí aṣọ,

Àwọn tó ń gbé ibẹ̀ sì máa kú bíi kòkòrò abìyẹ́ tó ń mùjẹ̀.

Àmọ́ ìgbàlà mi máa wà títí láé,+

Òdodo mi ò sì ní kùnà láéláé.*+

 7 Ẹ fetí sí mi, ẹ̀yin tó mọ òdodo,

Àwọn èèyàn tí òfin* mi wà lọ́kàn wọn.+

Ẹ má bẹ̀rù bí àwọn ẹni kíkú ṣe ń pẹ̀gàn yín,

Ẹ má sì jẹ́ kí èébú wọn kó jìnnìjìnnì bá yín.

 8 Torí pé òólá* máa jẹ wọ́n run bí aṣọ;

Òólá tó ń jẹ aṣọ* máa jẹ wọ́n run bí irun àgùntàn.+

Àmọ́ òdodo mi máa wà títí láé,

Ìgbàlà mi sì máa wà jálẹ̀ gbogbo ìran.”+

 9 Jí! Jí! Gbé agbára wọ̀,

Ìwọ apá Jèhófà! +

Jí, bíi ti àwọn ọjọ́ tó ti pẹ́, bíi ti àwọn ìran tó ti kọjá.

Ṣebí ìwọ lo fọ́ Ráhábù*+ sí wẹ́wẹ́,

Tí o gún ẹran ńlá inú òkun ní àgúnyọ?+

10 Ṣebí ìwọ lo mú kí òkun gbẹ, alagbalúgbú omi inú ibú?+

Ṣebí ìwọ lo sọ ibú òkun di ọ̀nà, tí àwọn tí a tún rà gbà sọdá?+

11 Àwọn tí Jèhófà rà pa dà máa pa dà.+

Wọ́n máa kígbe ayọ̀ wá sí Síónì,+

Ayọ̀ tí kò lópin sì máa dé wọn ládé.*+

Ìdùnnú àti ayọ̀ máa jẹ́ tiwọn,

Ẹ̀dùn ọkàn àti ìbànújẹ́ sì máa fò lọ.+

12 “Èmi fúnra mi ni Ẹni tó ń tù yín nínú.+

Ṣé ó wá yẹ kí ẹ máa bẹ̀rù ẹni kíkú tó máa kú+

Àti ọmọ aráyé tó máa rọ bíi koríko tútù?

13 Kí ló dé tí o gbàgbé Jèhófà Aṣẹ̀dá rẹ,+

Ẹni tó na ọ̀run,+ tó sì fi ìpìlẹ̀ ayé sọlẹ̀?

Ò ń bẹ̀rù ìbínú aninilára* ṣáá láti àárọ̀ ṣúlẹ̀,

Àfi bíi pé ó láṣẹ láti pa ọ́ run.

Ibo wá ni ìbínú aninilára wà?

14 Wọ́n máa tó dá ẹni tí wọ́n fi ẹ̀wọ̀n dè, tó sì tẹ̀ ba sílẹ̀;+

Kò ní kú, kò sì ní lọ sínú kòtò,

Oúnjẹ ò sì ní wọ́n ọn.

15 Àmọ́ èmi ni Jèhófà Ọlọ́run rẹ,

Ẹni tó ń ru òkun sókè, tó sì ń mú kí ìgbì rẹ̀ máa pariwo;+

Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun ni orúkọ rẹ̀.+

16 Màá fi ọ̀rọ̀ mi sí ẹnu rẹ,

Màá sì fi òjìji ọwọ́ mi bò ọ́,+

Kí n lè gbé ọ̀run kalẹ̀, kí n sì fi ìpìlẹ̀ ayé sọlẹ̀,+

Kí n sì sọ fún Síónì pé, ‘Èèyàn mi ni ọ́.’+

17 Jí! Jí! Dìde, ìwọ Jerúsálẹ́mù,+

Ìwọ tí o ti mu ife ìbínú Jèhófà láti ọwọ́ rẹ̀.

O ti mu látinú aago náà;

O ti mu ife tó ń múni ta gọ̀ọ́gọ̀ọ́ gbẹ.+

18 Ìkankan nínú gbogbo ọmọ tó bí kò sí níbẹ̀ láti darí rẹ̀,

Kò sì sí ìkankan nínú gbogbo ọmọ tó tọ́ dàgbà tó di ọwọ́ rẹ̀ mú.

19 Ohun méjì yìí ti dé bá ọ.

Ta ló máa bá ọ kẹ́dùn?

Ìparun àti ìsọdahoro, ebi àti idà!+

Ta ló máa tù ọ́ nínú?+

20 Àwọn ọmọ rẹ ti dákú.+

Wọ́n dùbúlẹ̀ sí gbogbo oríta* ojú ọ̀nà

Bí àgùntàn igbó tó wà nínú àwọ̀n.

Ìbínú Jèhófà kún inú wọn, ìbáwí Ọlọ́run rẹ.”

21 Torí náà, jọ̀ọ́, fetí sí èyí,

Ìwọ obìnrin tí ìyà ń jẹ, tó sì ti yó, àmọ́ tí kì í ṣe wáìnì ló mu.

22 Ohun tí Olúwa rẹ, Jèhófà sọ nìyí, Ọlọ́run rẹ, tó ń gbèjà àwọn èèyàn rẹ̀:

“Wò ó! Màá gba ife tó ń múni ta gọ̀ọ́gọ̀ọ́ kúrò lọ́wọ́ rẹ,+

Aago náà, ife ìbínú mi;

O ò ní mu ún mọ́ láé.+

23 Màá fi sí ọwọ́ àwọn tó ń dá ọ lóró,+

Àwọn tó sọ fún ọ* pé, ‘Tẹ̀ ba ká lè rìn lórí rẹ!’

O wá sọ ẹ̀yìn rẹ di ilẹ̀,

Bí ojú ọ̀nà tí wọ́n máa rìn kọjá.”

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́