ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Jeremáyà 46
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Jeremáyà

      • Àsọtẹ́lẹ̀ lórí Íjíbítì (1-26)

        • Nebukadinésárì yóò ṣẹ́gun Íjíbítì (13, 26)

      • Ìlérí tí Ọlọ́run ṣe fún Ísírẹ́lì (27, 28)

Jeremáyà 46:1

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jer 1:10

Jeremáyà 46:2

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “Nebukadirésárì,” ọ̀nà míì tí wọ́n ń gbà kọ orúkọ yìí.

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jer 25:15, 19; Isk 29:2; 32:2
  • +2Kr 35:20
  • +2Ọb 23:36; Jer 25:1; 36:1

Jeremáyà 46:3

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Apata kékeré tí àwọn tafàtafà sábà máa ń gbé dání.

Jeremáyà 46:4

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Irú èyí tí àwọn ọmọ ogun máa ń dé.

Jeremáyà 46:6

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Ọb 24:7

Jeremáyà 46:8

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Isk 29:3; 32:2

Jeremáyà 46:9

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “fi okùn sí.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Isk 27:2, 10
  • +Jẹ 10:6, 13; Isk 30:4, 5
  • +Ais 66:19

Jeremáyà 46:10

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ìpakúpa.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Ọb 24:7

Jeremáyà 46:11

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 37:25; Jer 8:22
  • +Isk 30:21

Jeremáyà 46:12

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Isk 32:9

Jeremáyà 46:13

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “Nebukadirésárì,” ọ̀nà míì tí wọ́n ń gbà kọ orúkọ yìí.

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jer 43:10; Isk 29:19; 30:10

Jeremáyà 46:14

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “Mémúfísì.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jer 44:1; Isk 29:10; 30:6
  • +Jer 43:4, 7; Isk 30:18

Jeremáyà 46:17

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “àkókò tí a yàn.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Isk 29:3

Jeremáyà 46:18

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ìyẹn, ẹni tó ṣẹ́gun Íjíbítì.

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Joṣ 19:17, 22; Ond 4:6; Sm 89:12
  • +1Ọb 18:42

Jeremáyà 46:19

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “Mémúfísì.”

  • *

    Tàbí kó jẹ́, “yóò di ahoro.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Isk 32:15

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    7/1/2003, ojú ìwé 32

Jeremáyà 46:21

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jer 46:5, 15

Jeremáyà 46:22

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “tó ń kó igi jọ.”

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    3/15/2007, ojú ìwé 11

Jeremáyà 46:24

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Isk 30:10

Jeremáyà 46:25

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ìyẹn, Tíbésì.

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Na 3:8
  • +Isk 30:14
  • +Ẹk 12:12; Ais 19:1; Jer 43:12, 13
  • +Jer 17:5; 42:14

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    7/1/2003, ojú ìwé 32

Jeremáyà 46:26

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ọkàn.”

  • *

    Ní Héb., “Nebukadirésárì,” ọ̀nà míì tí wọ́n ń gbà kọ orúkọ yìí.

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jer 43:10, 11; Isk 32:11
  • +Isk 29:13, 14

Jeremáyà 46:27

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “èso.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ais 41:13; 43:1, 2; 44:2
  • +Ais 11:11; Jer 50:19; Isk 39:27; Emọ 9:14; Sef 3:20
  • +Jer 23:3, 6; 30:10, 11

Jeremáyà 46:28

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “tọ́ ọ sọ́nà.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jer 25:9
  • +Jer 5:10; Emọ 9:8
  • +Jer 10:24

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ìmọ̀, ojú ìwé 148

Àwọn míì

Jer. 46:1Jer 1:10
Jer. 46:2Jer 25:15, 19; Isk 29:2; 32:2
Jer. 46:22Kr 35:20
Jer. 46:22Ọb 23:36; Jer 25:1; 36:1
Jer. 46:62Ọb 24:7
Jer. 46:8Isk 29:3; 32:2
Jer. 46:9Isk 27:2, 10
Jer. 46:9Jẹ 10:6, 13; Isk 30:4, 5
Jer. 46:9Ais 66:19
Jer. 46:102Ọb 24:7
Jer. 46:11Jẹ 37:25; Jer 8:22
Jer. 46:11Isk 30:21
Jer. 46:12Isk 32:9
Jer. 46:13Jer 43:10; Isk 29:19; 30:10
Jer. 46:14Jer 44:1; Isk 29:10; 30:6
Jer. 46:14Jer 43:4, 7; Isk 30:18
Jer. 46:17Isk 29:3
Jer. 46:18Joṣ 19:17, 22; Ond 4:6; Sm 89:12
Jer. 46:181Ọb 18:42
Jer. 46:19Isk 32:15
Jer. 46:21Jer 46:5, 15
Jer. 46:24Isk 30:10
Jer. 46:25Na 3:8
Jer. 46:25Isk 30:14
Jer. 46:25Ẹk 12:12; Ais 19:1; Jer 43:12, 13
Jer. 46:25Jer 17:5; 42:14
Jer. 46:26Jer 43:10, 11; Isk 32:11
Jer. 46:26Isk 29:13, 14
Jer. 46:27Ais 41:13; 43:1, 2; 44:2
Jer. 46:27Ais 11:11; Jer 50:19; Isk 39:27; Emọ 9:14; Sef 3:20
Jer. 46:27Jer 23:3, 6; 30:10, 11
Jer. 46:28Jer 25:9
Jer. 46:28Jer 5:10; Emọ 9:8
Jer. 46:28Jer 10:24
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
  • 1
  • 2
  • 3
  • 4
  • 5
  • 6
  • 7
  • 8
  • 9
  • 10
  • 11
  • 12
  • 13
  • 14
  • 15
  • 16
  • 17
  • 18
  • 19
  • 20
  • 21
  • 22
  • 23
  • 24
  • 25
  • 26
  • 27
  • 28
Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
Jeremáyà 46:1-28

Jeremáyà

46 Ọ̀rọ̀ tí Jèhófà sọ fún wòlíì Jeremáyà nípa àwọn orílẹ̀-èdè nìyí:+ 2 Sí Íjíbítì,+ nípa àwọn ọmọ ogun Fáráò Nékò  + ọba Íjíbítì, tí ó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ odò Yúfírétì, ẹni tí Nebukadinésárì* ọba Bábílónì ṣẹ́gun ní Kákémíṣì, ní ọdún kẹrin Jèhóákímù+ ọmọ Jòsáyà, ọba Júdà:

 3 “Ẹ to asà* àti apata ńlá,

Ẹ sì jáde lọ sójú ogun.

 4 Ẹ fi ìjánu sí ẹṣin, kí ẹ sì gùn ún, ẹ̀yin agẹṣin.

Ẹ lọ dúró sí àyè yín, kí ẹ sì dé akoto.*

Ẹ dán aṣóró, kí ẹ sì wọ ẹ̀wù irin.

 5 ‘Kí nìdí tí mo fi rí wọn tí jìnnìjìnnì bò wọ́n?

Wọ́n ń sá pa dà, àwọn jagunjagun wọn ni a ti lù bolẹ̀.

Wọ́n ti sá lọ tẹ̀rùtẹ̀rù, àwọn jagunjagun wọn kò sì bojú wẹ̀yìn.

Ìbẹ̀rù wà níbi gbogbo,’ ni Jèhófà wí.

 6 ‘Àwọn tí ẹsẹ̀ wọn yá nílẹ̀ kò lè sá lọ, àwọn jagunjagun kò sì lè sá àsálà.

Ní àríwá, lẹ́gbẹ̀ẹ́ odò Yúfírétì,

Wọ́n ti kọsẹ̀, wọ́n sì ti ṣubú.’+

 7 Ta ló ń bọ̀ yìí bí odò Náílì,

Bí odò tí omi rẹ̀ ń ru gùdù?

 8 Íjíbítì ń gòkè bọ̀ bí odò Náílì,+

Bí odò tí omi rẹ̀ ń ru gùdù,

Ó sì sọ pé, ‘Màá gòkè lọ, màá sì bo ilẹ̀ ayé.

Màá pa ìlú náà àti àwọn tó ń gbé inú rẹ̀ run.’

 9 Ẹ gòkè lọ, ẹ̀yin ẹṣin!

Ẹ sá eré àsápajúdé, ẹ̀yin kẹ̀kẹ́ ẹṣin!

Kí àwọn jagunjagun jáde lọ,

Kúṣì àti Pútì, tí wọ́n mọ apata lò,+

Pẹ̀lú àwọn Lúdímù,+ tí wọ́n mọ ọrun tẹ̀,* tí wọ́n sì mọ̀ ọ́n lò,+

10 “Ọjọ́ yẹn jẹ́ ti Olúwa Ọba Aláṣẹ, Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun, ọjọ́ ẹ̀san tó máa gbẹ̀san lára àwọn ọ̀tá rẹ̀. Idà máa pa wọ́n ní àpatẹ́rùn, á sì mu ẹ̀jẹ̀ wọn ní àmuyó, nítorí Olúwa Ọba Aláṣẹ, Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun, ní ẹbọ* kan ní ilẹ̀ àríwá lẹ́gbẹ̀ẹ́ odò Yúfírétì.+

11 Gòkè lọ sí Gílíádì láti mú básámù wá,+

Ìwọ wúńdíá ọmọbìnrin Íjíbítì.

Asán ni o sọ oògùn rẹ di púpọ̀,

Torí kò sí ìwòsàn fún ọ.+

12 Àwọn orílẹ̀-èdè ti gbọ́ nípa àbùkù rẹ,+

Igbe ẹkún rẹ sì ti kún ilẹ̀ náà.

Nítorí jagunjagun ń kọsẹ̀ lára jagunjagun,

Àwọn méjèèjì sì jọ ṣubú lulẹ̀.”

13 Ọ̀rọ̀ tí Jèhófà sọ fún wòlíì Jeremáyà nípa bí Nebukadinésárì* ọba Bábílónì ṣe máa wá pa ilẹ̀ Íjíbítì rẹ́ nìyí:+

14 “Sọ ọ́ ní Íjíbítì, sì kéde rẹ̀ ní Mígídólì.+

Kéde rẹ̀ ní Nófì* àti ní Tápánẹ́sì.+

Sọ pé, ‘Ẹ dúró sí àyè yín, kí ẹ sì múra sílẹ̀,

Nítorí idà kan máa pani run ní gbogbo àyíká yín.

15 Kí nìdí tí a fi gbá àwọn alágbára ọkùnrin yín lọ?

Wọn kò lè dúró,

Nítorí Jèhófà ti tì wọ́n ṣubú.

16 Iye àwọn tó ń kọsẹ̀, tí wọ́n sì ń ṣubú pọ̀ gan-an.

Ẹnì kìíní ń sọ fún ẹnì kejì rẹ̀ pé:

“Dìde! Jẹ́ kí a pa dà sọ́dọ̀ àwọn èèyàn wa àti sí ìlú ìbílẹ̀ wa

Nítorí idà tó ń hanni léèmọ̀.”’

17 Ibẹ̀ ni wọ́n ti kéde pé,

‘Fáráò ọba Íjíbítì jẹ́ ariwo lásán

Òun ló jẹ́ kí àǹfààní* bọ́.’+

18 ‘Bí mo ti wà láàyè,’ ni Ọba wí, ẹni tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun,

‘Ó* máa wọlé wá bíi Tábórì+ láàárín àwọn òkè

Àti bíi Kámẹ́lì+ lẹ́gbẹ̀ẹ́ òkun.

19 Di ẹrù tí o máa gbé lọ sí ìgbèkùn,

Ìwọ ọmọbìnrin tó ń gbé ní Íjíbítì.

Nítorí Nófì* á di ohun àríbẹ̀rù;

Wọ́n á sọ iná sí i,* ẹnikẹ́ni ò sì ní lè gbé ibẹ̀.+

20 Íjíbítì dà bí abo ọmọ màlúù tó lẹ́wà,

Àmọ́ kòkòrò tó ń tani máa wá bá a láti àríwá.

21 Kódà àwọn ọmọ ogun tí ó háyà tó wà láàárín rẹ̀ dà bí ọmọ màlúù àbọ́sanra,

Ṣùgbọ́n àwọn náà ti pẹ̀yìn dà, wọ́n sì jọ sá lọ.

Wọn kò lè dúró,+

Nítorí ọjọ́ àjálù wọn ti dé bá wọn,

Àkókò ìbẹ̀wò wọn.’

22 ‘Ìró rẹ̀ dà bíi ti ejò tó ń sá lọ,

Nítorí wọ́n ń fi àáké lé e tagbáratagbára,

Bí àwọn ọkùnrin tó ń gé igi.*

23 Wọ́n á gé igbó rẹ̀ lulẹ̀,’ ni Jèhófà wí, ‘bó tiẹ̀ dà bíi pé inú rẹ̀ kò ṣeé wọ̀.

Nítorí wọ́n pọ̀ ju eéṣú lọ, wọn ò sì níye.

24 Ojú máa ti ọmọbìnrin Íjíbítì.

A ó fà á lé ọwọ́ àwọn èèyàn àríwá.’+

25 “Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun, Ọlọ́run Ísírẹ́lì, sọ pé: ‘Wò ó, màá yíjú sí Ámọ́nì+ láti Nóò*+ àti sí Fáráò àti Íjíbítì àti àwọn ọlọ́run rẹ̀+ àti àwọn ọba rẹ̀, àní màá yíjú sí Fáráò àti gbogbo àwọn tí wọ́n gbẹ́kẹ̀ lé e.’+

26 “‘Màá fà wọ́n lé ọwọ́ àwọn tó fẹ́ gba ẹ̀mí* wọn, lé ọwọ́ Nebukadinésárì* ọba Bábílónì+ àti àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀. Lẹ́yìn náà, wọ́n á máa gbé inú rẹ̀ bíi ti àtijọ́,’ ni Jèhófà wí.+

27 ‘Ní tìrẹ, má fòyà, ìwọ Jékọ́bù ìránṣẹ́ mi,

Má sì jẹ́ kí ẹ̀rù bà ọ́, ìwọ Ísírẹ́lì.+

Nítorí màá gbà ọ́ láti ibi tó jìnnà réré

Àti àwọn ọmọ* rẹ láti oko ẹrú tí wọ́n wà.+

Jékọ́bù á pa dà, ara rẹ̀ á balẹ̀, kò ní rí ìyọlẹ́nu,

Ẹnì kankan ò sì ní dẹ́rù bà wọ́n.+

28 Torí náà, má fòyà, ìwọ Jékọ́bù ìránṣẹ́ mi,’ ni Jèhófà wí, ‘torí pé mo wà pẹ̀lú rẹ.

Màá pa gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè tí mo tú ọ ká sí àárín wọn run,+

Àmọ́ ní tìrẹ, mi ò ní pa ọ́ run.+

Mi ò ní bá ọ wí* kọjá ààlà,+

Mi ò sì ní ṣàìfi ìyà jẹ ọ́.’”

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́