ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Jeremáyà 31
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Jeremáyà

      • Àwọn tó ṣẹ́ kù ní Ísírẹ́lì á tún pa dà máa gbé ilẹ̀ wọn (1-30)

        • Réṣẹ́lì ń sunkún nítorí àwọn ọmọ rẹ̀ (15)

      • Májẹ̀mú tuntun (31-40)

Jeremáyà 31:1

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Le 26:12; Jer 30:22; 31:33

Jeremáyà 31:3

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “tí mò ń fi ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ hàn sí ọ.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Di 7:8

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Jeremáyà, ojú ìwé 143

Jeremáyà 31:4

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “máa jó lọ bí àwọn tó ń jó tẹ̀ríntẹ̀rín.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jer 33:7; Emọ 9:11
  • +Jer 30:18, 19

Jeremáyà 31:5

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Emọ 9:14; Mik 4:4
  • +Di 30:9; Ais 65:21, 22

Jeremáyà 31:6

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ais 2:3; Jer 50:4, 5

Jeremáyà 31:7

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Di 32:43; Ais 44:23
  • +Ais 1:9; Jer 23:3; Joẹ 2:32

Jeremáyà 31:8

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ais 43:6; Jer 3:12
  • +Di 30:4; Isk 20:34; 34:12
  • +Ais 35:6; 42:16
  • +Ẹsr 2:1, 64

Jeremáyà 31:9

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “àfonífojì.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jer 50:4
  • +Ais 35:7; 49:10
  • +Jẹ 48:14; Ẹk 4:22

Jeremáyà 31:10

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ais 11:11; 42:10
  • +Ais 40:11; Isk 34:11-13; Mik 2:12

Jeremáyà 31:11

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “gbà á pa dà.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ais 44:23; 48:20
  • +Ais 49:25

Jeremáyà 31:12

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “àwọn ohun rere látọ̀dọ̀.”

  • *

    Tàbí “Ọkàn wọn.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹsr 3:13; Sm 126:1; Ais 51:11
  • +Joẹ 3:18
  • +Ais 65:10
  • +Ais 58:11
  • +Ais 35:10

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Sún Mọ́ Jèhófà, ojú ìwé 278

Jeremáyà 31:13

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Sek 8:4
  • +Ẹsr 3:12
  • +Ais 51:3; 65:19

Jeremáyà 31:14

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “sísanra.”

  • *

    Tàbí “ọkàn àwọn àlùfáà.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Di 30:9; Ais 63:7

Jeremáyà 31:15

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ọmọ.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Joṣ 18:21, 25; Jer 40:1
  • +Ida 1:16
  • +Mt 2:16-18

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Jésù—Ọ̀nà, ojú ìwé 24

    Ilé Ìṣọ́,

    12/15/2014, ojú ìwé 21

    8/15/2011, ojú ìwé 10

    Jeremáyà, ojú ìwé 162

Jeremáyà 31:16

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹsr 1:5; Jer 23:3; Isk 11:17; Ho 1:11

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    12/15/2014, ojú ìwé 21

Jeremáyà 31:17

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jer 29:11
  • +Jer 46:27

Jeremáyà 31:18

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    4/1/2012, ojú ìwé 10-11

Jeremáyà 31:19

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Di 30:1-3
  • +Ẹsr 9:6

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    4/1/2012, ojú ìwé 11

Jeremáyà 31:20

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “ìfun.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jer 31:9; Ho 14:4
  • +Ho 11:8
  • +Di 32:36; Mik 7:18

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    4/1/2012, ojú ìwé 11

    11/1/1994, ojú ìwé 12

    Jeremáyà, ojú ìwé 181

Jeremáyà 31:21

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ais 62:10
  • +Ais 35:8

Jeremáyà 31:23

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ais 1:26
  • +Sek 8:3

Jeremáyà 31:24

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jer 33:12; Isk 36:10, 11

Jeremáyà 31:25

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ọkàn.”

  • *

    Tàbí “ọkàn.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Sm 107:9

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Jeremáyà, ojú ìwé 81-82

Jeremáyà 31:27

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “èso.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Di 30:9; Isk 36:9; Ho 2:23

Jeremáyà 31:28

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jer 44:27; 45:4
  • +Sm 102:16; 147:2; Jer 24:6

Jeremáyà 31:29

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “eyín wọn kò mú.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Isk 18:2-4

Jeremáyà 31:31

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Mt 26:27, 28; Lk 22:20; 1Kọ 11:25; Heb 8:8-12

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    3/15/2010, ojú ìwé 26-27

    2/1/1998, ojú ìwé 12

    Jeremáyà, ojú ìwé 169-170

    Àìléwu Kárí-Ayé, ojú ìwé 100-101, 106-107

    “Ete aiyeraiye,” ojú ìwé 158-160

Jeremáyà 31:32

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí kó jẹ́, “ọkọ wọn.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 19:5
  • +Isk 16:59

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Jeremáyà, ojú ìwé 169-170

    Ilé Ìṣọ́,

    2/1/1998, ojú ìwé 12

    Àìléwu Kárí-Ayé, ojú ìwé 100-101

Jeremáyà 31:33

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Isk 11:19
  • +Heb 10:16
  • +Jer 24:7; 30:22

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Jeremáyà, ojú ìwé 173-175, 179-180

    Ilé Ìṣọ́,

    3/15/2007, ojú ìwé 11

    3/15/1998, ojú ìwé 13-14

    2/1/1998, ojú ìwé 14-15, 19-20

    Àìléwu Kárí-Ayé, ojú ìwé 113-114

Jeremáyà 31:34

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ais 54:13; Jo 17:3
  • +Ais 11:9; Hab 2:14
  • +Jer 33:8; 50:20; Mt 26:27, 28; Heb 8:10-12; 9:15; 10:17

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Sún Mọ́ Jèhófà, ojú ìwé 266-267

    Ilé Ìṣọ́,

    8/15/2012, ojú ìwé 30

    2/1/1998, ojú ìwé 15-16, 19-20

    12/1/1997, ojú ìwé 12-13

    Jeremáyà, ojú ìwé 170-173, 177-178, 179-181

    Àìléwu Kárí-Ayé, ojú ìwé 116-118, 119-120

Jeremáyà 31:35

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “pa àṣẹ.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ais 51:15

Jeremáyà 31:36

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ais 54:10; Jer 33:20, 21

Jeremáyà 31:37

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jer 30:11

Jeremáyà 31:38

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ne 12:27; Ais 44:28; Jer 30:18
  • +Ne 3:1; Sek 14:10
  • +2Kr 26:9

Jeremáyà 31:39

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Sek 1:16

Jeremáyà 31:40

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “pẹ̀tẹ́lẹ̀.”

  • *

    Tàbí “eérú ọlọ́ràá,” ìyẹn, eérú tí ọ̀rá tí wọ́n fi rúbọ ti rin.

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Sa 15:23; 2Ọb 23:6; Jo 18:1
  • +Ne 3:28
  • +Joẹ 3:17

Àwọn míì

Jer. 31:1Le 26:12; Jer 30:22; 31:33
Jer. 31:3Di 7:8
Jer. 31:4Jer 33:7; Emọ 9:11
Jer. 31:4Jer 30:18, 19
Jer. 31:5Emọ 9:14; Mik 4:4
Jer. 31:5Di 30:9; Ais 65:21, 22
Jer. 31:6Ais 2:3; Jer 50:4, 5
Jer. 31:7Di 32:43; Ais 44:23
Jer. 31:7Ais 1:9; Jer 23:3; Joẹ 2:32
Jer. 31:8Ais 43:6; Jer 3:12
Jer. 31:8Di 30:4; Isk 20:34; 34:12
Jer. 31:8Ais 35:6; 42:16
Jer. 31:8Ẹsr 2:1, 64
Jer. 31:9Jer 50:4
Jer. 31:9Ais 35:7; 49:10
Jer. 31:9Jẹ 48:14; Ẹk 4:22
Jer. 31:10Ais 11:11; 42:10
Jer. 31:10Ais 40:11; Isk 34:11-13; Mik 2:12
Jer. 31:11Ais 44:23; 48:20
Jer. 31:11Ais 49:25
Jer. 31:12Ẹsr 3:13; Sm 126:1; Ais 51:11
Jer. 31:12Joẹ 3:18
Jer. 31:12Ais 65:10
Jer. 31:12Ais 58:11
Jer. 31:12Ais 35:10
Jer. 31:13Sek 8:4
Jer. 31:13Ẹsr 3:12
Jer. 31:13Ais 51:3; 65:19
Jer. 31:14Di 30:9; Ais 63:7
Jer. 31:15Joṣ 18:21, 25; Jer 40:1
Jer. 31:15Ida 1:16
Jer. 31:15Mt 2:16-18
Jer. 31:16Ẹsr 1:5; Jer 23:3; Isk 11:17; Ho 1:11
Jer. 31:17Jer 29:11
Jer. 31:17Jer 46:27
Jer. 31:19Di 30:1-3
Jer. 31:19Ẹsr 9:6
Jer. 31:20Jer 31:9; Ho 14:4
Jer. 31:20Ho 11:8
Jer. 31:20Di 32:36; Mik 7:18
Jer. 31:21Ais 62:10
Jer. 31:21Ais 35:8
Jer. 31:23Ais 1:26
Jer. 31:23Sek 8:3
Jer. 31:24Jer 33:12; Isk 36:10, 11
Jer. 31:25Sm 107:9
Jer. 31:27Di 30:9; Isk 36:9; Ho 2:23
Jer. 31:28Jer 44:27; 45:4
Jer. 31:28Sm 102:16; 147:2; Jer 24:6
Jer. 31:29Isk 18:2-4
Jer. 31:31Mt 26:27, 28; Lk 22:20; 1Kọ 11:25; Heb 8:8-12
Jer. 31:32Ẹk 19:5
Jer. 31:32Isk 16:59
Jer. 31:33Isk 11:19
Jer. 31:33Heb 10:16
Jer. 31:33Jer 24:7; 30:22
Jer. 31:34Ais 54:13; Jo 17:3
Jer. 31:34Ais 11:9; Hab 2:14
Jer. 31:34Jer 33:8; 50:20; Mt 26:27, 28; Heb 8:10-12; 9:15; 10:17
Jer. 31:35Ais 51:15
Jer. 31:36Ais 54:10; Jer 33:20, 21
Jer. 31:37Jer 30:11
Jer. 31:382Kr 26:9
Jer. 31:38Ne 12:27; Ais 44:28; Jer 30:18
Jer. 31:38Ne 3:1; Sek 14:10
Jer. 31:39Sek 1:16
Jer. 31:402Sa 15:23; 2Ọb 23:6; Jo 18:1
Jer. 31:40Ne 3:28
Jer. 31:40Joẹ 3:17
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
  • 1
  • 2
  • 3
  • 4
  • 5
  • 6
  • 7
  • 8
  • 9
  • 10
  • 11
  • 12
  • 13
  • 14
  • 15
  • 16
  • 17
  • 18
  • 19
  • 20
  • 21
  • 22
  • 23
  • 24
  • 25
  • 26
  • 27
  • 28
  • 29
  • 30
  • 31
  • 32
  • 33
  • 34
  • 35
  • 36
  • 37
  • 38
  • 39
  • 40
Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
Jeremáyà 31:1-40

Jeremáyà

31 “Ní àkókò yẹn,” ni Jèhófà wí, “màá di Ọlọ́run gbogbo ìdílé Ísírẹ́lì, wọ́n á sì di èèyàn mi.”+

 2 Ohun tí Jèhófà sọ nìyí:

“Àwọn tó bọ́ lọ́wọ́ idà rí ojú rere ní aginjù

Nígbà tí Ísírẹ́lì ń rìn lọ sí ibi ìsinmi rẹ̀.”

 3 Jèhófà ti fara hàn mí láti ọ̀nà jíjìn, ó sì sọ pé:

“Ìfẹ́ tí mo ní sí ọ jẹ́ ìfẹ́ ayérayé.

Ìdí nìyẹn tí mo fi fà ọ́ mọ́ra pẹ̀lú ìfẹ́ tí kì í yẹ̀.*+

 4 Síbẹ̀ náà, màá tún ọ kọ́ bí ilé, wàá sì dà bí ilé tí a tún kọ́.+

Ìwọ wúńdíá Ísírẹ́lì, wàá tún pa dà mú ìlù tanboríìnì rẹ

Wàá sì máa jó lọ tayọ̀tayọ̀.*+

 5 Wàá tún pa dà gbin àwọn ọgbà àjàrà sórí àwọn òkè Samáríà;+

Àwọn tó gbìn wọ́n á sì gbádùn èso wọn.+

 6 Nítorí ọjọ́ ń bọ̀, nígbà tí àwọn olùṣọ́ tó wà lórí àwọn òkè Éfúrémù máa ké jáde pé:

‘Ẹ dìde, ẹ jẹ́ ká lọ sí Síónì, sọ́dọ̀ Jèhófà Ọlọ́run wa.’”+

 7 Nítorí ohun tí Jèhófà sọ nìyí:

“Ẹ fi ìdùnnú kọrin sí Jékọ́bù.

Ẹ sì kígbe ayọ̀ nítorí ẹ ti ga ju àwọn orílẹ̀-èdè lọ.+

Ẹ kéde rẹ̀; ẹ yin Ọlọ́run, kí ẹ sì sọ pé,

‘Jèhófà, gba àwọn èèyàn rẹ là, àwọn tó ṣẹ́ kù ní Ísírẹ́lì.’+

 8 Màá mú wọn pa dà wá láti ilẹ̀ àríwá.+

Màá sì kó wọn jọ láti ibi tó jìnnà jù lọ láyé.+

Àwọn afọ́jú àti àwọn arọ máa wà lára wọn,+

Aboyún àti ẹni tó ń rọbí, gbogbo wọn pa pọ̀.

Bí ìjọ ńlá ni wọ́n máa pa dà sí ibí yìí.+

 9 Wọ́n á wá pẹ̀lú ẹkún.+

Màá máa darí wọn bí wọ́n ṣe ń wá ojú rere.

Màá ṣamọ̀nà wọn lọ sí ìṣàn* omi,+

Lórí ọ̀nà tó tẹ́jú tí wọn ò ti ní kọsẹ̀.

Nítorí èmi ni Bàbá Ísírẹ́lì, Éfúrémù sì ni àkọ́bí mi.”+

10 Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ Jèhófà, ẹ̀yin orílẹ̀-èdè,

Ẹ sì kéde rẹ̀ láàárín àwọn erékùṣù tó jìnnà réré pé:+

“Ẹni tó tú Ísírẹ́lì ká máa kó o jọ.

Á máa bójú tó o bí olùṣọ́ àgùntàn ṣe ń bójú tó agbo ẹran rẹ̀.+

11 Nítorí Jèhófà máa ra Jékọ́bù pa dà+

Á sì gbà á* lọ́wọ́ ẹni tó lágbára jù ú lọ.+

12 Wọ́n á wá, wọ́n á sì kígbe ayọ̀ ní ibi gíga Síónì+

Inú wọn á dùn nítorí oore* Jèhófà,

Nítorí ọkà àti wáìnì tuntun+ pẹ̀lú òróró,

Nítorí àwọn ọmọ inú agbo ẹran àti ọ̀wọ́ ẹran.+

Wọ́n* á dà bí ọgbà tí a bomi rin dáadáa,+

Wọn kò sì ní ráágó mọ́.”+

13 “Ní àkókò yẹn, wúńdíá á máa jó ijó ayọ̀,

Àwọn ọ̀dọ́kùnrin àti àwọn àgbà ọkùnrin á máa jó pa pọ̀.+

Màá sọ ọ̀fọ̀ wọn di ìdùnnú.+

Màá tù wọ́n nínú, màá sì fún wọn ní ayọ̀ dípò ẹ̀dùn ọkàn tí wọ́n ní.+

14 Màá fi ọ̀pọ̀ nǹkan* tẹ́ àwọn àlùfáà* lọ́rùn,

Oore mi á sì tẹ́ àwọn èèyàn mi lọ́rùn,”+ ni Jèhófà wí.

15 “Ohun tí Jèhófà sọ nìyí:

‘A gbọ́ ohùn kan ní Rámà,+ ìdárò àti ẹkún kíkorò:

Réṣẹ́lì ń sunkún nítorí àwọn ọmọkùnrin* rẹ̀.+

Wọ́n tù ú nínú nítorí àwọn ọmọ rẹ̀, àmọ́ kò gbà,

Torí pé wọn kò sí mọ́.’”+

16 Ohun tí Jèhófà sọ nìyí:

“‘Má sunkún mọ́, má sì da omi lójú mọ́,

Nítorí èrè wà fún iṣẹ́ rẹ,’ ni Jèhófà wí.

‘Wọ́n á pa dà láti ilẹ̀ ọ̀tá.’+

17 ‘Ìrètí wà fún ọ ní ọjọ́ ọ̀la,’+ ni Jèhófà wí.

‘Àwọn ọmọ rẹ á sì pa dà sí ilẹ̀ wọn.’”+

18 “Mo ti gbọ́ tí Éfúrémù ń kérora,

‘O ti tọ́ mi sọ́nà, mo sì ti gba ìtọ́sọ́nà,

Bí ọmọ màlúù tí a kò fi iṣẹ́ kọ́.

Mú mi pa dà, màá sì ṣe tán láti yí pa dà,

Nítorí ìwọ ni Jèhófà Ọlọ́run mi.

19 Torí pé lẹ́yìn tí mo pa dà, mo kẹ́dùn;+

Lẹ́yìn tí wọ́n ti fi yé mi, mo gbá itan mi tẹ̀dùntẹ̀dùn.

Ojú tì mí, ẹ̀tẹ́ sì bá mi,+

Nítorí mo ti ru ẹ̀gàn ìgbà èwe mi.’”

20 “Ǹjẹ́ Éfúrémù kì í ṣe ọmọ mi àtàtà, ọmọ tí mo nífẹ̀ẹ́?+

Torí bí mo ṣe ń sọ̀rọ̀ sí i tó, síbẹ̀ mo ṣì ń rántí rẹ̀.

Ìdí nìyẹn tí ọkàn* mi fi gbé sókè nítorí rẹ̀.+

Ó sì dájú pé màá ṣàánú rẹ̀,” ni Jèhófà wí.+

21 “Ri àwọn àmì ojú ọ̀nà mọ́lẹ̀ fún ará rẹ,

Ri àwọn òpó àmì mọ́lẹ̀.+

Fiyè sí òpópónà, ọ̀nà tí o máa gbà.+

Pa dà, ìwọ wúńdíá Ísírẹ́lì, pa dà wá sí àwọn ìlú rẹ.

22 Ìgbà wo lo máa ṣiyèméjì dà, ìwọ aláìṣòótọ́ ọmọbìnrin?

Nítorí Jèhófà ti dá ohun tuntun kan sí ayé:

Obìnrin kan á máa fìtara lé ọkùnrin kan kiri.”

23 Ohun tí Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun, Ọlọ́run Ísírẹ́lì sọ nìyí: “Wọ́n á tún ọ̀rọ̀ yìí sọ ní ilẹ̀ Júdà àti ní àwọn ìlú rẹ̀, nígbà tí mo bá kó àwọn èèyàn rẹ̀ tó wà lóko ẹrú pa dà: ‘Kí Jèhófà bù kún ọ, ìwọ ibùgbé òdodo,+ ìwọ òkè mímọ́.’+ 24 Inú rẹ̀ ni Júdà àti gbogbo àwọn ìlú rẹ̀ á jọ máa gbé, àwọn àgbẹ̀ àti àwọn tó ń da agbo ẹran.+ 25 Nítorí ẹni* tí àárẹ̀ mú ni màá tẹ́ lọ́rùn, màá sì pèsè fún gbogbo ẹni* tó jẹ́ aláìní.”+

26 Bí mo ṣe gbọ́ èyí ni mo jí, mo la ojú mi, oorun mi sì dùn mọ́ mi.

27 “Wò ó! Ọjọ́ ń bọ̀,” ni Jèhófà wí, “tí màá sọ àtọmọdọ́mọ* ilé Ísírẹ́lì àti ilé Júdà di púpọ̀, tí màá sì sọ àwọn ẹran agbéléjẹ̀ wọn di púpọ̀.”+

28 “Bí mo ṣe kíyè sí wọn láti fà wọ́n tu, láti ya wọ́n lulẹ̀, láti fà wọ́n ya, láti pa wọ́n run àti láti ṣe wọ́n léṣe,+ bẹ́ẹ̀ ni màá kíyè sí wọn láti kọ́ wọn bí ilé àti láti gbìn wọ́n,”+ ni Jèhófà wí. 29 “Ní àkókò yẹn, wọn kò tún ní sọ pé, ‘Àwọn baba jẹ èso àjàrà kíkan, ṣùgbọ́n àwọn ọmọ ni eyín kan.’*+ 30 Àmọ́ nígbà náà, kálukú máa kú nítorí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀. Ẹni tó bá sì jẹ èso àjàrà kíkan ni eyín máa kan.”

31 “Wò ó! Ọjọ́ ń bọ̀,” ni Jèhófà wí, “tí màá bá ilé Ísírẹ́lì àti ilé Júdà dá májẹ̀mú tuntun.+ 32 Kò ní dà bíi májẹ̀mú tí mo bá àwọn baba ńlá wọn dá ní ọjọ́ tí mo dì wọ́n lọ́wọ́ mú láti mú wọn kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì,+ ‘májẹ̀mú mi tí wọ́n dà,+ bó tilẹ̀ jẹ́ pé èmi ni ọ̀gá wọn tòótọ́,’* ni Jèhófà wí.”

33 “Nítorí májẹ̀mú tí màá bá ilé Ísírẹ́lì dá lẹ́yìn ìgbà yẹn nìyí,” ni Jèhófà wí. “Màá fi òfin mi sínú wọn,+ inú ọkàn wọn sì ni màá kọ ọ́ sí.+ Màá di Ọlọ́run wọn, wọ́n á sì di èèyàn mi.”+

34 “Kálukú wọn kò tún ní máa kọ́ ẹnì kejì rẹ̀ àti arákùnrin rẹ̀ mọ́ pé, ‘Ẹ mọ Jèhófà!’+ nítorí gbogbo wọn á mọ̀ mí, látorí ẹni tó kéré jù lọ dórí ẹni tó tóbi jù lọ láàárín wọn,”+ ni Jèhófà wí. “Nítorí màá dárí àṣìṣe wọn jì wọ́n, mi ò sì ní rántí ẹ̀ṣẹ̀ wọn mọ́.”+

35 Ohun tí Jèhófà sọ nìyí,

Ẹni tó ń mú kí oòrùn máa tan ìmọ́lẹ̀ ní ọ̀sán,

Tó sì ṣe òfin* pé kí òṣùpá àti àwọn ìràwọ̀ máa tàn ní òru,

Ẹni tó ń ru òkun sókè, tó sì ń mú kí ìgbì rẹ̀ máa pariwo,

Ẹni tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun:+

36 “‘Bí àwọn ìlànà yìí bá yí pa dà

Nìkan ni àtọmọdọ́mọ Ísírẹ́lì kò fi ní jẹ́ orílẹ̀-èdè níwájú mi mọ́,’ ni Jèhófà wí.”+

37 Ohun tí Jèhófà sọ nìyí: “‘Àyàfi bí a bá lè díwọ̀n ọ̀run lókè, tí a sì lè wá ìpìlẹ̀ ayé kàn nísàlẹ̀, ni màá tó kọ gbogbo àtọmọdọ́mọ Ísírẹ́lì sílẹ̀ torí àwọn ohun tí wọ́n ti ṣe,’ ni Jèhófà wí.”+

38 “Wò ó! Ọjọ́ ń bọ̀,” ni Jèhófà wí, “nígbà tí wọ́n á kọ́ ìlú+ fún Jèhófà láti Ilé Gogoro Hánánélì+ dé Ẹnubodè Igun.+ 39 Okùn ìdíwọ̀n+ máa jáde lọ tààrà sí òkè Gárébù, á sì yíjú sí Góà. 40 Gbogbo àfonífojì* àwọn òkú àti ti eérú* pẹ̀lú gbogbo ilẹ̀ onípele títí dé Àfonífojì Kídírónì,+ títí lọ dé igun Ẹnubodè Ẹṣin,+ lápá ìlà oòrùn, yóò jẹ́ ohun mímọ́ fún Jèhófà.+ A kò ní fà á tu láé, bẹ́ẹ̀ ni a kò ní ya á lulẹ̀.”

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́