ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Àìsáyà 41
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Àìsáyà

      • Aṣẹ́gun kan láti ìlà oòrùn (1-7)

      • Ọlọ́run yan Ísírẹ́lì pé kó jẹ́ ìránṣẹ́ òun (8-20)

        • “Ábúráhámù ọ̀rẹ́ mi” (8)

      • Ó pe àwọn ọlọ́run míì níjà (21-29)

Àìsáyà 41:1

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “Ẹ dákẹ́ níwájú mi.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ais 41:21

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kejì, ojú ìwé 17

Àìsáyà 41:2

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “láti ìlà oòrùn.”

  • *

    Ìyẹn, láti sìn Ín.

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ais 44:28; 46:11; Ifi 16:12
  • +Ais 45:1

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kejì, ojú ìwé 18-20

Àìsáyà 41:3

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kejì, ojú ìwé 18-20

Àìsáyà 41:4

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ais 43:10; 44:6; 48:12; Ifi 1:8
  • +Ais 46:4; Mal 3:6; Jem 1:17

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kejì, ojú ìwé 18-20

Àìsáyà 41:5

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kejì, ojú ìwé 20-22

Àìsáyà 41:6

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kejì, ojú ìwé 20-22

Àìsáyà 41:7

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ìyẹn, hámà ńlá tí àwọn alágbẹ̀dẹ máa ń lò.

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ais 44:12; 46:6

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kejì, ojú ìwé 20, 22

Àìsáyà 41:8

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “Èso.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 19:5, 6; Le 25:42
  • +Di 7:6; Sm 33:12
  • +2Kr 20:7; Jem 2:23

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    2/15/2014, ojú ìwé 21-22

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kejì, ojú ìwé 22-23

    “Ete aiyeraiye,” ojú ìwé 87-88

Àìsáyà 41:9

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Sm 107:2, 3
  • +Ais 43:10
  • +1Sa 12:22; Jer 33:25, 26

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kejì, ojú ìwé 22-23

Àìsáyà 41:10

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Di 20:1; Sm 46:1; Ro 8:31
  • +Ais 60:19, 20
  • +Di 33:27; Sm 115:9

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àlàyé Àwọn Ẹsẹ Bíbélì, àpilẹ̀kọ 5

    Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!, ẹ̀kọ́ 8

    Ilé Ìṣọ́ (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́),

    1/2019, ojú ìwé 2-7

    Ilé Ìṣọ́ (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́),

    4/2018, ojú ìwé 16

    Ilé Ìṣọ́ (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́),

    7/2016, ojú ìwé 18

    Ilé Ìṣọ́,

    1/1/2012, ojú ìwé 18

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kejì, ojú ìwé 22-23

Àìsáyà 41:11

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ais 45:24
  • +Ais 40:17; 60:12

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́ (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́),

    1/2019, ojú ìwé 7

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kejì, ojú ìwé 23-24

Àìsáyà 41:12

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ais 54:17

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kejì, ojú ìwé 23-24

Àìsáyà 41:13

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Di 33:29

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!, ẹ̀kọ́ 8

    Ilé Ìṣọ́ (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́),

    1/2019, ojú ìwé 3

    Ilé Ìṣọ́ (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́),

    7/2016, ojú ìwé 18

    Ilé Ìṣọ́,

    1/1/2012, ojú ìwé 18

    10/1/2006, ojú ìwé 30

    12/15/2004, ojú ìwé 17-18

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kejì, ojú ìwé 23-24

Àìsáyà 41:14

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ìyẹn, ẹni tó rẹlẹ̀ tí kò sì lè gbèjà ara rẹ̀.

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Di 7:7
  • +Ais 43:14; 47:4

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́ (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́),

    1/2019, ojú ìwé 3

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kejì, ojú ìwé 23-24

Àìsáyà 41:15

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ìyẹn, èèpo fúlẹ́fúlẹ́ ara ọkà.

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Mik 4:13

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kejì, ojú ìwé 24-25

Àìsáyà 41:16

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ais 25:9
  • +Ais 12:6

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kejì, ojú ìwé 24-25

Àìsáyà 41:17

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Di 28:48; Emọ 8:11
  • +Ais 30:19; 55:1
  • +Sm 94:14; Ais 42:16; Heb 13:5

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kejì, ojú ìwé 25-26

Àìsáyà 41:18

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ìyẹn, koríko etí omi.

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ais 30:25
  • +Joẹ 3:18
  • +Sm 107:35

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kejì, ojú ìwé 25-26

Àìsáyà 41:19

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ais 32:14, 15; 60:21
  • +Ais 51:3; 55:13

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kejì, ojú ìwé 25-26

Àìsáyà 41:20

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Isk 39:28

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kejì, ojú ìwé 25-26

Àìsáyà 41:21

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kejì, ojú ìwé 26-28

Àìsáyà 41:22

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “àkọ́kọ́.”

  • *

    Tàbí “fọkàn sí i.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ais 42:9; 46:9, 10; 48:5

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kejì, ojú ìwé 26-28

    Ilé-Ìṣọ́nà,

    6/15/1993, ojú ìwé 14

Àìsáyà 41:23

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ais 44:6, 7
  • +Jer 10:5

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kejì, ojú ìwé 26-28

Àìsáyà 41:24

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ais 44:10; Jer 10:14, 15
  • +Di 7:26; 27:15; Sm 115:4, 8

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kejì, ojú ìwé 26-28

Àìsáyà 41:25

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “láti ìlà oòrùn.”

  • *

    Tàbí “ìjòyè.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ais 44:28; 45:1; Jer 51:28, 29
  • +Ais 46:11; Ifi 16:12
  • +Mik 7:10

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kejì, ojú ìwé 28-29

Àìsáyà 41:26

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ais 43:9; 44:7; 45:21
  • +Hab 2:18, 19

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kejì, ojú ìwé 29

Àìsáyà 41:27

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ais 43:10
  • +Ẹsr 1:1, 2; Ais 40:9

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kejì, ojú ìwé 29

Àìsáyà 41:28

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kejì, ojú ìwé 29

Àìsáyà 41:29

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ohun tí kò sí rárá.”

  • *

    Tàbí “ère dídà.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Sm 115:4-8; Ais 44:9; 1Kọ 8:4

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kejì, ojú ìwé 29

Àwọn míì

Àìsá. 41:1Ais 41:21
Àìsá. 41:2Ais 44:28; 46:11; Ifi 16:12
Àìsá. 41:2Ais 45:1
Àìsá. 41:4Ais 43:10; 44:6; 48:12; Ifi 1:8
Àìsá. 41:4Ais 46:4; Mal 3:6; Jem 1:17
Àìsá. 41:7Ais 44:12; 46:6
Àìsá. 41:8Ẹk 19:5, 6; Le 25:42
Àìsá. 41:8Di 7:6; Sm 33:12
Àìsá. 41:82Kr 20:7; Jem 2:23
Àìsá. 41:9Sm 107:2, 3
Àìsá. 41:9Ais 43:10
Àìsá. 41:91Sa 12:22; Jer 33:25, 26
Àìsá. 41:10Di 20:1; Sm 46:1; Ro 8:31
Àìsá. 41:10Ais 60:19, 20
Àìsá. 41:10Di 33:27; Sm 115:9
Àìsá. 41:11Ais 45:24
Àìsá. 41:11Ais 40:17; 60:12
Àìsá. 41:12Ais 54:17
Àìsá. 41:13Di 33:29
Àìsá. 41:14Di 7:7
Àìsá. 41:14Ais 43:14; 47:4
Àìsá. 41:15Mik 4:13
Àìsá. 41:16Ais 25:9
Àìsá. 41:16Ais 12:6
Àìsá. 41:17Di 28:48; Emọ 8:11
Àìsá. 41:17Ais 30:19; 55:1
Àìsá. 41:17Sm 94:14; Ais 42:16; Heb 13:5
Àìsá. 41:18Ais 30:25
Àìsá. 41:18Joẹ 3:18
Àìsá. 41:18Sm 107:35
Àìsá. 41:19Ais 32:14, 15; 60:21
Àìsá. 41:19Ais 51:3; 55:13
Àìsá. 41:20Isk 39:28
Àìsá. 41:22Ais 42:9; 46:9, 10; 48:5
Àìsá. 41:23Ais 44:6, 7
Àìsá. 41:23Jer 10:5
Àìsá. 41:24Ais 44:10; Jer 10:14, 15
Àìsá. 41:24Di 7:26; 27:15; Sm 115:4, 8
Àìsá. 41:25Ais 44:28; 45:1; Jer 51:28, 29
Àìsá. 41:25Ais 46:11; Ifi 16:12
Àìsá. 41:25Mik 7:10
Àìsá. 41:26Ais 43:9; 44:7; 45:21
Àìsá. 41:26Hab 2:18, 19
Àìsá. 41:27Ais 43:10
Àìsá. 41:27Ẹsr 1:1, 2; Ais 40:9
Àìsá. 41:29Sm 115:4-8; Ais 44:9; 1Kọ 8:4
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
  • 1
  • 2
  • 3
  • 4
  • 5
  • 6
  • 7
  • 8
  • 9
  • 10
  • 11
  • 12
  • 13
  • 14
  • 15
  • 16
  • 17
  • 18
  • 19
  • 20
  • 21
  • 22
  • 23
  • 24
  • 25
  • 26
  • 27
  • 28
  • 29
Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
Àìsáyà 41:1-29

Àìsáyà

41 “Ẹ dákẹ́, kí ẹ sì fetí sí mi,* ẹ̀yin erékùṣù;

Kí àwọn orílẹ̀-èdè pa dà ní agbára.

Kí wọ́n sún mọ́ tòsí; kí wọ́n wá sọ̀rọ̀.+

Ẹ jẹ́ ká kóra jọ fún ìdájọ́.

 2 Ta ló ti gbé ẹnì kan dìde láti ibi tí oòrùn ti ń yọ,*+

Tó pè é nínú òdodo wá síbi ẹsẹ̀ Rẹ̀,*

Láti fa àwọn orílẹ̀-èdè lé e lọ́wọ́,

Kó sì mú kó tẹ àwọn ọba lórí ba?+

Ta ló ń sọ wọ́n di eruku níwájú idà rẹ̀,

Bí àgékù pòròpórò tí atẹ́gùn ń gbé kiri níwájú ọfà rẹ̀?

 3 Ó ń lé wọn, ohunkóhun ò sì dí i lọ́wọ́

Lójú ọ̀nà tí kò fẹsẹ̀ tẹ̀ rí.

 4 Ta ló ṣe èyí? Iṣẹ́ ọwọ́ ta sì ni,

Tó ń pe àwọn ìran láti ìbẹ̀rẹ̀?

Èmi Jèhófà, ni Ẹni Àkọ́kọ́;+

Èmi kan náà ni mo sì wà pẹ̀lú àwọn tó kẹ́yìn.”+

 5 Àwọn erékùṣù rí i, ẹ̀rù sì bà wọ́n.

Àwọn ìkángun ayé bẹ̀rẹ̀ sí í wárìrì.

Wọ́n sún mọ́ tòsí, wọ́n sì bọ́ síwájú.

 6 Kálukú ń ran ẹnì kejì rẹ̀ lọ́wọ́,

Wọ́n ń sọ fún àwọn arákùnrin wọn pé: “Ẹ jẹ́ alágbára.”

 7 Torí náà, oníṣẹ́ ọnà ń fún oníṣẹ́ irin+ lókun;

Ẹni tó ń fi òòlù irin* lu nǹkan di pẹlẹbẹ

Ń fún ẹni tó ń fi òòlù lu nǹkan lórí irin lókun.

Ó ń sọ nípa ohun tí wọ́n jó pọ̀ pé: “Ó dáa.”

Wọ́n wá fi ìṣó kàn án, kó má bàa ṣubú.

 8 “Àmọ́ ìwọ Ísírẹ́lì ni ìránṣẹ́ mi,+

Ìwọ Jékọ́bù, ẹni tí mo yàn,+

Ọmọ* Ábúráhámù ọ̀rẹ́ mi,+

 9 Ìwọ tí mo mú láti àwọn ìkángun ayé,+

Ìwọ tí mo pè láti àwọn apá ibi tó jìnnà jù níbẹ̀.

Mo sọ fún ọ pé, ‘Ìwọ ni ìránṣẹ́ mi;+

Mo ti yàn ọ́; Mi ò kọ̀ ọ́.+

10 Má bẹ̀rù, torí mo wà pẹ̀lú rẹ.+

Má ṣàníyàn, torí èmi ni Ọlọ́run rẹ.+

Màá fún ọ lókun, àní, màá ràn ọ́ lọ́wọ́,+

Ní tòótọ́, màá fi ọwọ́ ọ̀tún òdodo mi dì ọ́ mú ṣinṣin.’

11 Wò ó! Ojú máa ti gbogbo àwọn tó ń bínú sí ọ, wọ́n sì máa tẹ́.+

Àwọn tó ń bá ọ jà máa di ẹni tí kò já mọ́ nǹkan kan, wọ́n sì máa ṣègbé.+

12 O máa wá àwọn tó ń bá ọ jà, àmọ́ o ò ní rí wọn;

Àwọn tó ń bá ọ jagun máa dà bí ohun tí kò sí, bí ohun tí kò sí rárá.+

13 Torí pé èmi Jèhófà Ọlọ́run rẹ ń di ọwọ́ ọ̀tún rẹ mú,

Ẹni tó ń sọ fún ọ pé, ‘Má bẹ̀rù. Màá ràn ọ́ lọ́wọ́.’+

14 Má bẹ̀rù, ìwọ Jékọ́bù kòkòrò mùkúlú,*+

Ẹ̀yin ọkùnrin Ísírẹ́lì, màá ràn yín lọ́wọ́,” ni Jèhófà, Olùtúnrà yín,+ Ẹni Mímọ́ Ísírẹ́lì wí.

15 “Wò ó! Mo ti sọ ọ́ di ohun tí wọ́n fi ń pakà,+

Ohun tuntun tó ní eyín olójú méjì tí wọ́n fi ń pakà.

O máa tẹ àwọn òkè ńlá mọ́lẹ̀, o máa fọ́ wọn túútúú,

O sì máa ṣe àwọn òkè kéékèèké bí ìyàngbò.*

16 O máa fẹ́ wọn bí ọkà,

Atẹ́gùn sì máa gbé wọn lọ;

Ìjì máa tú wọn ká.

Inú rẹ máa dùn torí Jèhófà,+

O sì máa fi Ẹni Mímọ́ Ísírẹ́lì yangàn.”+

17 “Àwọn aláìní àti àwọn tálákà ń wá omi, àmọ́ kò sí rárá.

Òùngbẹ ti mú kí ahọ́n wọn gbẹ.+

Èmi Jèhófà máa dá wọn lóhùn.+

Èmi Ọlọ́run Ísírẹ́lì ò ní fi wọ́n sílẹ̀.+

18 Màá mú kí odò ṣàn lórí àwọn òkè tí nǹkan ò hù sí,+

Màá sì mú kí omi sun ní àwọn pẹ̀tẹ́lẹ̀.+

Màá sọ aginjù di adágún omi tí esùsú* kún inú rẹ̀,

Màá sì sọ ilẹ̀ tí kò lómi di orísun omi.  +

19 Màá gbin igi kédárì sínú aṣálẹ̀,

Màá gbin igi bọn-ọ̀n-ní, igi mátílì àti igi ahóyaya síbẹ̀.+

Màá gbin igi júnípà sí aṣálẹ̀ tó tẹ́jú,

Pẹ̀lú igi áàṣì àti igi sípírẹ́sì,+

20 Kí gbogbo èèyàn lè rí i, kí wọ́n sì mọ̀,

Kí wọ́n fiyè sí i, kó sì yé wọn,

Pé ọwọ́ Jèhófà ló ṣe èyí,

Ẹni Mímọ́ Ísírẹ́lì ló sì dá a.”+

21 “Ẹ ro ẹjọ́ yín,” ni Jèhófà wí.

“Ẹ gbèjà ara yín,” ni Ọba Jékọ́bù wí.

22 “Ẹ mú ẹ̀rí wá, kí ẹ sì sọ ohun tó máa ṣẹlẹ̀ fún wa.

Ẹ sọ àwọn ohun àtijọ́* fún wa,

Ká lè ronú nípa wọn,* ká sì mọ ibi tí wọ́n máa já sí.

Tàbí kí ẹ kéde àwọn ohun tó ń bọ̀ fún wa.+

23 Ẹ sọ àwọn ohun tó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú fún wa,

Ká lè mọ̀ pé ọlọ́run ni yín.+

Àní, ẹ ṣe nǹkan kan, ì báà jẹ́ rere tàbí búburú,

Kó lè yà wá lẹ́nu tí a bá rí i.+

24 Ẹ wò ó! Ohun tí kò sí ni yín,

Iṣẹ́ ọwọ́ yín kò sì já mọ́ nǹkan kan.+

Ohun ìríra ni ẹnikẹ́ni tó bá yàn yín.+

25 Mo ti gbé ẹnì kan dìde láti àríwá, ó sì máa wá,+

Ẹnì kan láti ibi tí oòrùn ti ń yọ*+ tó máa ké pe orúkọ mi.

Ó máa tẹ àwọn alákòóso* mọ́lẹ̀ bíi pé amọ̀ ni wọ́n,+

Bí amọ̀kòkò tó ń tẹ amọ̀ rírin mọ́lẹ̀.

26 Ta ló sọ èyí láti ìbẹ̀rẹ̀, ká lè mọ̀,

Tàbí láti ìgbà àtijọ́, ká lè sọ pé, ‘Ó tọ̀nà’?+

Lóòótọ́, kò sí ẹni tó sọ ọ́!

Kò sí ẹni tó kéde rẹ̀!

Kò sí ẹni tó gbọ́ ohunkóhun látọ̀dọ̀ rẹ!”+

27 Èmi ni mo kọ́kọ́ sọ fún Síónì pé: “Wò ó! Àwọn nìyí!”+

Màá sì rán ẹni tó ń mú ìròyìn ayọ̀ wá sí Jerúsálẹ́mù.+

28 Àmọ́ mò ń wò, kò sì sí ẹnì kankan;

Kò sí ìkankan nínú wọn tó ń gbani nímọ̀ràn.

Mo sì ń sọ fún wọn ṣáá pé kí wọ́n fèsì.

29 Wò ó! Gbogbo wọn jẹ́ ẹ̀tàn.*

Iṣẹ́ wọn kò já mọ́ nǹkan kan.

Afẹ́fẹ́ lásán àti ohun tí kò sí rárá ni àwọn ère onírin* wọn.+

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́