ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Léfítíkù 21
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Léfítíkù

      • Kí àwọn àlùfáà jẹ́ mímọ́ kí wọ́n má sì di ẹlẹ́gbin (1-9)

      • Àlùfáà àgbà ò gbọ́dọ̀ sọ ara rẹ̀ di aláìmọ́ (10-15)

      • Àwọn àlùfáà ò gbọ́dọ̀ ní àbùkù kankan lára (16-24)

Léfítíkù 21:1

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ọkàn.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Nọ 19:14

Léfítíkù 21:5

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Di 14:1
  • +Le 19:27, 28

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àwọn Ìtẹ̀jáde Tá A Tọ́ka sí Nínú Ìwé Ìpàdé, 1/2021,

Léfítíkù 21:6

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “búrẹ́dì,” ó ń tọ́ka sí àwọn ẹbọ.

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 29:44
  • +Le 18:21; 19:12; 22:32
  • +Ais 52:11; 1Pe 1:15, 16

Léfítíkù 21:7

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Le 19:29
  • +Di 24:1; Isk 44:22

Léfítíkù 21:8

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 28:41
  • +Ẹk 28:36; Le 11:45; 20:7, 8

Léfítíkù 21:9

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Le 20:14

Léfítíkù 21:10

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “fi kún ọwọ́ rẹ̀.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Le 8:12
  • +Ẹk 28:2; 29:29; Le 16:32
  • +Jẹ 37:34; Le 10:6

Léfítíkù 21:11

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ọkàn èyíkéyìí tó ti kú.” Ní ẹsẹ yìí, ọ̀rọ̀ Hébérù náà neʹphesh jẹ mọ́ ọ̀rọ̀ Hébérù tó túmọ̀ sí “òkú.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Nọ 6:7; 19:11, 14

Léfítíkù 21:12

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Le 10:7
  • +Le 8:12

Léfítíkù 21:13

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Isk 44:22

Léfítíkù 21:15

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “èso.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹsr 9:2

Léfítíkù 21:17

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “èso.”

Léfítíkù 21:18

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “tàbí tí imú rẹ̀ là.”

Léfítíkù 21:20

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí kó jẹ́, “ẹni tó rù kan eegun.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Di 23:1

Léfítíkù 21:21

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “èso.”

Léfítíkù 21:22

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Le 2:10; 6:14, 16; 24:8, 9; Nọ 18:9
  • +Le 22:10; Nọ 18:19

Léfítíkù 21:23

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 30:6
  • +Ẹk 38:1
  • +Ẹk 25:8
  • +Ẹk 28:41

Àwọn míì

Léf. 21:1Nọ 19:14
Léf. 21:5Di 14:1
Léf. 21:5Le 19:27, 28
Léf. 21:6Ẹk 29:44
Léf. 21:6Le 18:21; 19:12; 22:32
Léf. 21:6Ais 52:11; 1Pe 1:15, 16
Léf. 21:7Le 19:29
Léf. 21:7Di 24:1; Isk 44:22
Léf. 21:8Ẹk 28:41
Léf. 21:8Ẹk 28:36; Le 11:45; 20:7, 8
Léf. 21:9Le 20:14
Léf. 21:10Le 8:12
Léf. 21:10Ẹk 28:2; 29:29; Le 16:32
Léf. 21:10Jẹ 37:34; Le 10:6
Léf. 21:11Nọ 6:7; 19:11, 14
Léf. 21:12Le 10:7
Léf. 21:12Le 8:12
Léf. 21:13Isk 44:22
Léf. 21:15Ẹsr 9:2
Léf. 21:20Di 23:1
Léf. 21:22Le 2:10; 6:14, 16; 24:8, 9; Nọ 18:9
Léf. 21:22Le 22:10; Nọ 18:19
Léf. 21:23Ẹk 30:6
Léf. 21:23Ẹk 38:1
Léf. 21:23Ẹk 25:8
Léf. 21:23Ẹk 28:41
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
  • 1
  • 2
  • 3
  • 4
  • 5
  • 6
  • 7
  • 8
  • 9
  • 10
  • 11
  • 12
  • 13
  • 14
  • 15
  • 16
  • 17
  • 18
  • 19
  • 20
  • 21
  • 22
  • 23
  • 24
Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
Léfítíkù 21:1-24

Léfítíkù

21 Jèhófà wá sọ fún Mósè pé: “Sọ fún àwọn àlùfáà, àwọn ọmọ Áárónì pé, ‘Ẹnikẹ́ni nínú yín ò gbọ́dọ̀ sọ ara rẹ̀ di aláìmọ́ torí ẹni* tó kú láàárín àwọn èèyàn rẹ̀.+ 2 Àmọ́ ó lè ṣe bẹ́ẹ̀ tí ẹni náà bá jẹ́ mọ̀lẹ́bí rẹ̀ tó sún mọ́ ọn, ìyá rẹ̀, bàbá rẹ̀, ọmọkùnrin rẹ̀, ọmọbìnrin rẹ̀ tàbí arákùnrin rẹ̀, 3 ó sì lè fi arábìnrin rẹ̀ sọ ara rẹ̀ di aláìmọ́, tó bá jẹ́ wúńdíá tó wà nítòsí rẹ̀, tí kò sì tíì lọ́kọ. 4 Kò gbọ́dọ̀ fi obìnrin tó fẹ́ ọkọ láàárín àwọn èèyàn rẹ̀ sọ ara rẹ̀ di ẹlẹ́gbin tàbí sọ ara rẹ̀ di aláìmọ́. 5 Kí wọ́n má ṣe fá orí wọn,+ kí wọ́n má sì fá eteetí irùngbọ̀n wọn tàbí kí wọ́n fi nǹkan ya ara wọn.+ 6 Kí wọ́n jẹ́ mímọ́ sí Ọlọ́run wọn,+ kí wọ́n má sì sọ orúkọ Ọlọ́run wọn di aláìmọ́,+ torí àwọn ló ń mú àwọn ọrẹ àfinásun sí Jèhófà wá, oúnjẹ* Ọlọ́run wọn, wọ́n gbọ́dọ̀ jẹ́ mímọ́.+ 7 Wọn ò gbọ́dọ̀ fẹ́ aṣẹ́wó,+ obìnrin tí wọ́n ti bá sùn tàbí obìnrin tí ọkọ rẹ̀ kọ̀ sílẹ̀,+ torí àlùfáà jẹ́ mímọ́ sí Ọlọ́run rẹ̀. 8 Kí o sọ ọ́ di mímọ́,+ torí òun ló ń gbé oúnjẹ Ọlọ́run rẹ wá. Kó jẹ́ mímọ́ sí ọ, torí èmi Jèhófà, tó ń sọ yín di mímọ́, jẹ́ mímọ́.+

9 “‘Tí ọmọbìnrin àlùfáà bá ṣe aṣẹ́wó, tó tipa bẹ́ẹ̀ sọ ara rẹ̀ di aláìmọ́, bàbá rẹ̀ ló sọ di aláìmọ́. Kí ẹ fi iná sun+ ọmọbìnrin náà.

10 “‘Ẹni tó jẹ́ àlùfáà àgbà nínú àwọn arákùnrin rẹ̀, tí wọ́n da òróró àfiyanni+ sí lórí, tí wọ́n sì ti fi iṣẹ́ lé lọ́wọ́* kó lè wọ aṣọ àlùfáà,+ kò gbọ́dọ̀ fi orí rẹ̀ sílẹ̀ láìtọ́jú tàbí kó ya aṣọ rẹ̀.+ 11 Kó má ṣe sún mọ́ òkú ẹnikẹ́ni;*+ tó bá tiẹ̀ jẹ́ bàbá rẹ̀ tàbí ìyá rẹ̀, kò gbọ́dọ̀ fi wọ́n sọ ara rẹ̀ di aláìmọ́. 12 Kò gbọ́dọ̀ jáde kúrò nínú ibi mímọ́, kò sì gbọ́dọ̀ sọ ibi mímọ́ Ọlọ́run rẹ̀ di aláìmọ́,+ torí àmì ìyàsímímọ́, òróró àfiyanni ti Ọlọ́run rẹ̀,+ wà lórí rẹ̀. Èmi ni Jèhófà.

13 “‘Obìnrin tó jẹ́ wúńdíá+ ni kó fi ṣe aya. 14 Kó má ṣe fẹ́ opó, obìnrin tí ọkọ rẹ̀ kọ̀ sílẹ̀, ẹni tí wọ́n ti bá sùn tàbí aṣẹ́wó; àmọ́ kó mú wúńdíá látinú àwọn èèyàn rẹ̀, kó fi ṣe aya. 15 Kó má sọ ọmọ* rẹ̀ di aláìmọ́ láàárín àwọn èèyàn rẹ̀,+ torí èmi ni Jèhófà, tó ń sọ ọ́ di mímọ́.’”

16 Jèhófà ń bá ọ̀rọ̀ tó ń sọ fún Mósè lọ pé: 17 “Sọ fún Áárónì pé, ‘Ọkùnrin èyíkéyìí tó bá ní àbùkù lára nínú àwọn ọmọ* rẹ jálẹ̀ àwọn ìran wọn kò gbọ́dọ̀ sún mọ́ tòsí láti gbé oúnjẹ Ọlọ́run rẹ̀ wá. 18 Tí ọkùnrin èyíkéyìí bá ní àbùkù lára, kó má ṣe sún mọ́ tòsí: ọkùnrin tó fọ́jú tàbí tó yarọ tàbí tí ojú rẹ̀ ní àbùkù* tàbí tí apá tàbí ẹsẹ̀ rẹ̀ kan gùn jù, 19 tàbí ọkùnrin tí egungun ẹsẹ̀ rẹ̀ tàbí egungun ọwọ́ rẹ̀ kán, 20 abuké tàbí aràrá* tàbí ọkùnrin tí ojú ń dùn tàbí tó ní ifo tàbí làpálàpá tàbí tí nǹkan ṣe kórópọ̀n rẹ̀.+ 21 Ọkùnrin èyíkéyìí tó ní àbùkù lára nínú àwọn ọmọ* àlùfáà Áárónì ò gbọ́dọ̀ sún mọ́ tòsí láti gbé àwọn ọrẹ àfinásun sí Jèhófà wá. Kò gbọ́dọ̀ sún mọ́ tòsí láti gbé oúnjẹ Ọlọ́run rẹ̀ wá torí ó ní àbùkù lára. 22 Ó lè jẹ oúnjẹ Ọlọ́run rẹ̀, látinú àwọn ohun mímọ́ jù lọ+ àti àwọn ohun mímọ́.+ 23 Àmọ́, kó má ṣe sún mọ́ aṣọ ìdábùú,+ kó má sì sún mọ́ pẹpẹ,+ torí ó ní àbùkù lára; kó má sì sọ ibi mímọ́+ mi di aláìmọ́, torí èmi ni Jèhófà tó ń sọ wọ́n di mímọ́.’”+

24 Mósè sì bá Áárónì àti àwọn ọmọ rẹ̀ àti gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sọ̀rọ̀.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́