ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Nọ́ńbà 4
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Nọ́ńbà

      • Iṣẹ́ àwọn ọmọ Kóhátì (1-20)

      • Iṣẹ́ àwọn ọmọ Gẹ́ṣónì (21-28)

      • Iṣẹ́ àwọn ọmọ Mérárì (29-33)

      • Àròpọ̀ iye àwọn tí wọ́n forúkọ wọn sílẹ̀ (34-49)

Nọ́ńbà 4:2

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Nọ 3:19, 27

Nọ́ńbà 4:3

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Kr 23:3; Lk 3:23
  • +Nọ 8:25, 26
  • +Nọ 4:30; 1Kr 6:48

Nọ́ńbà 4:4

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Nọ 3:30, 31; 4:15

Nọ́ńbà 4:5

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “ibùdó.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 26:31; 40:3; Le 16:2
  • +Ẹk 25:10

Nọ́ńbà 4:6

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 25:13

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    10/15/2001, ojú ìwé 31

Nọ́ńbà 4:7

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 25:23, 24
  • +Ẹk 25:29
  • +Le 24:5, 6

Nọ́ńbà 4:8

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 25:28

Nọ́ńbà 4:9

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ẹ̀mú.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 25:31
  • +Ẹk 25:37
  • +Ẹk 25:38

Nọ́ńbà 4:11

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 30:1; 37:25, 26
  • +Ẹk 30:5

Nọ́ńbà 4:12

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Nọ 3:30, 31

Nọ́ńbà 4:13

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “eérú ọlọ́ràá,” ìyẹn, eérú tí ọ̀rá tí wọ́n fi rúbọ ti rin.

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Le 6:12

Nọ́ńbà 4:14

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 27:3
  • +Ẹk 27:6

Nọ́ńbà 4:15

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “ibùdó.”

  • *

    Ní Héb., “Ẹrù.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Nọ 4:5
  • +Nọ 7:6-9; 1Kr 15:2
  • +2Sa 6:6, 7

Nọ́ńbà 4:16

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Nọ 3:32
  • +Ẹk 27:20
  • +Ẹk 30:34, 35
  • +Ẹk 30:23-25

Nọ́ńbà 4:18

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Nọ 3:27

Nọ́ńbà 4:19

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Nọ 4:4

Nọ́ńbà 4:20

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 19:21; 1Sa 6:19

Nọ́ńbà 4:22

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Nọ 3:21

Nọ́ńbà 4:24

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Nọ 3:25, 26

Nọ́ńbà 4:25

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “aṣọ ìdábùú.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 26:1
  • +Ẹk 26:7, 14
  • +Ẹk 26:36

Nọ́ńbà 4:26

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “aṣọ ìdábùú.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 27:9
  • +Ẹk 27:16

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àwọn Ìtẹ̀jáde Tá A Tọ́ka sí Nínú Ìwé Ìpàdé, 1/2021,

Nọ́ńbà 4:27

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Nọ 3:21, 23

Nọ́ńbà 4:28

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Nọ 3:25, 26
  • +Ẹk 6:23; Nọ 4:33; 7:8

Nọ́ńbà 4:29

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 6:19; Nọ 3:33

Nọ́ńbà 4:31

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Nọ 3:36, 37
  • +Ẹk 26:15
  • +Ẹk 26:26
  • +Ẹk 26:37; 36:38
  • +Ẹk 26:19; 38:27

Nọ́ńbà 4:32

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 27:10
  • +Ẹk 27:11
  • +Ẹk 27:19

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àwọn Ìtẹ̀jáde Tá A Tọ́ka sí Nínú Ìwé Ìpàdé, 1/2021,

Nọ́ńbà 4:33

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Nọ 3:33
  • +Nọ 4:28

Nọ́ńbà 4:34

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Nọ 1:16
  • +Nọ 3:19, 27

Nọ́ńbà 4:35

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Nọ 4:47; 8:25, 26

Nọ́ńbà 4:36

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Nọ 3:27, 28

Nọ́ńbà 4:37

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Nọ 3:15

Nọ́ńbà 4:38

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Nọ 3:21

Nọ́ńbà 4:40

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Nọ 3:21, 22

Nọ́ńbà 4:41

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Nọ 4:22, 23

Nọ́ńbà 4:43

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Nọ 8:25, 26

Nọ́ńbà 4:44

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Nọ 3:33, 34

Nọ́ńbà 4:45

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Nọ 4:29

Nọ́ńbà 4:47

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Nọ 4:15, 24-26, 31-33

Nọ́ńbà 4:48

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Nọ 3:39

Àwọn míì

Nọ́ń. 4:2Nọ 3:19, 27
Nọ́ń. 4:31Kr 23:3; Lk 3:23
Nọ́ń. 4:3Nọ 8:25, 26
Nọ́ń. 4:3Nọ 4:30; 1Kr 6:48
Nọ́ń. 4:4Nọ 3:30, 31; 4:15
Nọ́ń. 4:5Ẹk 26:31; 40:3; Le 16:2
Nọ́ń. 4:5Ẹk 25:10
Nọ́ń. 4:6Ẹk 25:13
Nọ́ń. 4:7Ẹk 25:23, 24
Nọ́ń. 4:7Ẹk 25:29
Nọ́ń. 4:7Le 24:5, 6
Nọ́ń. 4:8Ẹk 25:28
Nọ́ń. 4:9Ẹk 25:31
Nọ́ń. 4:9Ẹk 25:37
Nọ́ń. 4:9Ẹk 25:38
Nọ́ń. 4:11Ẹk 30:1; 37:25, 26
Nọ́ń. 4:11Ẹk 30:5
Nọ́ń. 4:12Nọ 3:30, 31
Nọ́ń. 4:13Le 6:12
Nọ́ń. 4:14Ẹk 27:3
Nọ́ń. 4:14Ẹk 27:6
Nọ́ń. 4:15Nọ 4:5
Nọ́ń. 4:15Nọ 7:6-9; 1Kr 15:2
Nọ́ń. 4:152Sa 6:6, 7
Nọ́ń. 4:16Nọ 3:32
Nọ́ń. 4:16Ẹk 27:20
Nọ́ń. 4:16Ẹk 30:34, 35
Nọ́ń. 4:16Ẹk 30:23-25
Nọ́ń. 4:18Nọ 3:27
Nọ́ń. 4:19Nọ 4:4
Nọ́ń. 4:20Ẹk 19:21; 1Sa 6:19
Nọ́ń. 4:22Nọ 3:21
Nọ́ń. 4:24Nọ 3:25, 26
Nọ́ń. 4:25Ẹk 26:1
Nọ́ń. 4:25Ẹk 26:7, 14
Nọ́ń. 4:25Ẹk 26:36
Nọ́ń. 4:26Ẹk 27:9
Nọ́ń. 4:26Ẹk 27:16
Nọ́ń. 4:27Nọ 3:21, 23
Nọ́ń. 4:28Nọ 3:25, 26
Nọ́ń. 4:28Ẹk 6:23; Nọ 4:33; 7:8
Nọ́ń. 4:29Ẹk 6:19; Nọ 3:33
Nọ́ń. 4:31Nọ 3:36, 37
Nọ́ń. 4:31Ẹk 26:15
Nọ́ń. 4:31Ẹk 26:26
Nọ́ń. 4:31Ẹk 26:37; 36:38
Nọ́ń. 4:31Ẹk 26:19; 38:27
Nọ́ń. 4:32Ẹk 27:10
Nọ́ń. 4:32Ẹk 27:11
Nọ́ń. 4:32Ẹk 27:19
Nọ́ń. 4:33Nọ 3:33
Nọ́ń. 4:33Nọ 4:28
Nọ́ń. 4:34Nọ 1:16
Nọ́ń. 4:34Nọ 3:19, 27
Nọ́ń. 4:35Nọ 4:47; 8:25, 26
Nọ́ń. 4:36Nọ 3:27, 28
Nọ́ń. 4:37Nọ 3:15
Nọ́ń. 4:38Nọ 3:21
Nọ́ń. 4:40Nọ 3:21, 22
Nọ́ń. 4:41Nọ 4:22, 23
Nọ́ń. 4:43Nọ 8:25, 26
Nọ́ń. 4:44Nọ 3:33, 34
Nọ́ń. 4:45Nọ 4:29
Nọ́ń. 4:47Nọ 4:15, 24-26, 31-33
Nọ́ń. 4:48Nọ 3:39
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
  • 1
  • 2
  • 3
  • 4
  • 5
  • 6
  • 7
  • 8
  • 9
  • 10
  • 11
  • 12
  • 13
  • 14
  • 15
  • 16
  • 17
  • 18
  • 19
  • 20
  • 21
  • 22
  • 23
  • 24
  • 25
  • 26
  • 27
  • 28
  • 29
  • 30
  • 31
  • 32
  • 33
  • 34
  • 35
  • 36
  • 37
  • 38
  • 39
  • 40
  • 41
  • 42
  • 43
  • 44
  • 45
  • 46
  • 47
  • 48
  • 49
Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
Nọ́ńbà 4:1-49

Nọ́ńbà

4 Lẹ́yìn náà, Jèhófà sọ fún Mósè àti Áárónì pé: 2 “Ẹ ka àwọn ọmọ Kóhátì+ lára àwọn ọmọ Léfì, ní ìdílé-ìdílé àti agbo ilé bàbá wọn, 3 gbogbo àwọn tó jẹ́ ẹni ọgbọ̀n (30)+ ọdún sí àádọ́ta (50) ọdún,+ tí wọ́n wà lára àwọn tí a yàn pé kí wọ́n máa ṣiṣẹ́ nínú àgọ́ ìpàdé.+

4 “Èyí ni iṣẹ́ àwọn ọmọ Kóhátì nínú àgọ́ ìpàdé.+ Ohun mímọ́ jù lọ ni: 5 Tí àwọn èèyàn* náà bá fẹ́ gbéra, kí Áárónì àti àwọn ọmọ rẹ̀ wọlé, kí wọ́n tú aṣọ ìdábùú+ kúrò, kí wọ́n sì fi bo àpótí+ Ẹ̀rí. 6 Kí wọ́n fi awọ séálì bò ó, kí wọ́n na aṣọ tó jẹ́ kìkì àwọ̀ búlúù sórí rẹ̀, kí wọ́n sì ki àwọn ọ̀pá tí wọ́n á fi gbé e+ bọ̀ ọ́.

7 “Kí wọ́n tún na aṣọ aláwọ̀ búlúù bo tábìlì búrẹ́dì àfihàn,+ kí wọ́n sì kó àwọn àwo ìjẹun sórí rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ife, àwọn abọ́ àti àwọn ṣágo ọrẹ ohun mímu;+ kí búrẹ́dì+ ọrẹ máa wà lórí rẹ̀ nígbà gbogbo. 8 Kí wọ́n na aṣọ aláwọ̀ rírẹ̀dòdò sórí wọn, kí wọ́n fi awọ séálì bò ó, kí wọ́n sì ki àwọn ọ̀pá tí wọ́n á fi gbé e+ bọ̀ ọ́. 9 Kí wọ́n wá mú aṣọ aláwọ̀ búlúù, kí wọ́n sì fi bo ọ̀pá fìtílà+ tí wọ́n fi ń tan iná,+ pẹ̀lú àwọn fìtílà rẹ̀, àwọn ìpaná* rẹ̀, àwọn ìkóná rẹ̀+ àti gbogbo ohun èlò rẹ̀ tí wọ́n ń fi òróró sí láti máa fi tàn án. 10 Kí wọ́n fi awọ séálì wé e pẹ̀lú gbogbo ohun èlò rẹ̀, kí wọ́n sì gbé e sórí ọ̀pá gbọọrọ tí wọ́n á fi gbé e. 11 Kí wọ́n na aṣọ aláwọ̀ búlúù sórí pẹpẹ wúrà,+ kí wọ́n fi awọ séálì bò ó, kí wọ́n sì ki àwọn ọ̀pá tí wọ́n á fi gbé e  + bọ̀ ọ́. 12 Kí wọ́n wá kó gbogbo ohun èlò+ tí wọ́n fi ń ṣiṣẹ́, èyí tí wọ́n máa ń lò déédéé nínú ibi mímọ́, kí wọ́n kó o sínú aṣọ aláwọ̀ búlúù, kí wọ́n fi awọ séálì bò ó, kí wọ́n sì gbé e sórí ọ̀pá gbọọrọ tí wọ́n á fi gbé e.

13 “Kí wọ́n kó eérú* kúrò nínú pẹpẹ,+ kí wọ́n sì na aṣọ tí wọ́n fi òwú aláwọ̀ pọ́pù ṣe sórí rẹ̀. 14 Kí wọ́n kó gbogbo ohun èlò tí wọ́n fi ń ṣiṣẹ́ níbi pẹpẹ náà sórí rẹ̀: àwọn ìkóná, àwọn àmúga, àwọn ṣọ́bìrì àti àwọn abọ́, gbogbo ohun èlò pẹpẹ;+ kí wọ́n fi awọ séálì bò ó, kí wọ́n sì ki àwọn ọ̀pá+ tí wọ́n á fi gbé e bọ̀ ọ́.

15 “Áárónì àti àwọn ọmọ rẹ̀ gbọ́dọ̀ ti bo ibi mímọ́+ náà tán àti gbogbo ohun èlò ibi mímọ́ náà nígbà tí àwọn èèyàn* náà bá fẹ́ gbéra. Kí àwọn ọmọ Kóhátì wá wọlé wá gbé e,+ àmọ́ wọn ò gbọ́dọ̀ fara kan ibi mímọ́ kí wọ́n má bàa kú.+ Ojúṣe* àwọn ọmọ Kóhátì nínú àgọ́ ìpàdé nìyí.

16 “Élíásárì+ ọmọ àlùfáà Áárónì ló ń bójú tó òróró tí wọ́n fi ń tan iná,+ tùràrí onílọ́fínńdà,+ ọrẹ ọkà ìgbà gbogbo àti òróró àfiyanni.+ Òun ló ń bójú tó gbogbo àgọ́ ìjọsìn àti gbogbo ohun tó wà nínú rẹ̀, títí kan ibi mímọ́ àti àwọn ohun èlò rẹ̀.”

17 Jèhófà ń bá ọ̀rọ̀ tó ń sọ fún Mósè àti Áárónì lọ pé: 18 “Ẹ má ṣe jẹ́ kí ẹ̀yà ìdílé àwọn ọmọ Kóhátì+ pa run láàárín àwọn ọmọ Léfì. 19 Ohun tí ẹ máa ṣe fún wọn nìyí kí wọ́n lè máa wà láàyè, kí wọ́n má sì kú torí pé wọ́n sún mọ́ àwọn ohun mímọ́ jù lọ.+ Kí Áárónì àti àwọn ọmọ rẹ̀ wọlé, kí wọ́n yan iṣẹ́ kálukú àti ohun tó máa gbé fún un. 20 Wọn ò gbọ́dọ̀ wọlé wá wo àwọn ohun mímọ́, ì báà jẹ́ fírí, àìjẹ́ bẹ́ẹ̀, wọ́n máa kú.”+

21 Jèhófà wá sọ fún Mósè pé: 22 “Ka àwọn ọmọ Gẹ́ṣónì,+ gẹ́gẹ́ bí agbo ilé bàbá wọn àti ní ìdílé-ìdílé. 23 Kí o forúkọ wọn sílẹ̀, gbogbo àwọn tó jẹ́ ẹni ọgbọ̀n (30) ọdún sí àádọ́ta (50) ọdún, tí wọ́n wà lára àwọn tí a yàn pé kí wọ́n máa ṣiṣẹ́ nínú àgọ́ ìpàdé. 24 Iṣẹ́ tí ìdílé àwọn ọmọ Gẹ́ṣónì á máa ṣe àtàwọn ohun tí wọ́n á máa gbé+ nìyí: 25 Kí wọ́n máa gbé aṣọ àgọ́+ ti àgọ́ ìjọsìn, àgọ́ ìpàdé, ìbòrí rẹ̀ àti ìbòrí tí wọ́n fi awọ séálì ṣe tó wà lókè rẹ̀,+ aṣọ* tí wọ́n ta sí ẹnu ọ̀nà àgọ́ ìpàdé,+ 26 àwọn aṣọ ìdábùú tí wọ́n ta sí àgbàlá,+ aṣọ* tí wọ́n ta sí ẹnu ọ̀nà àgbàlá+ tó yí àgọ́ ìjọsìn àti pẹpẹ ká, àwọn okùn àgọ́ wọn àti gbogbo ohun èlò wọn pẹ̀lú gbogbo ohun tí wọ́n fi ń ṣiṣẹ́ níbẹ̀. Iṣẹ́ tí wọ́n á máa ṣe nìyí. 27 Kí Áárónì àti àwọn ọmọ rẹ̀ máa bójú tó gbogbo iṣẹ́ àti ẹrù àwọn ọmọ Gẹ́ṣónì;+ kí ẹ yan gbogbo ẹrù yìí fún wọn pé kó jẹ́ ojúṣe wọn. 28 Èyí ni iṣẹ́ tí ìdílé àwọn ọmọ Gẹ́ṣónì á máa ṣe nínú àgọ́ ìpàdé,+ Ítámárì+ ọmọ àlùfáà Áárónì ni yóò sì máa darí iṣẹ́ wọn.

29 “Ní ti àwọn ọmọ Mérárì,+ kí o forúkọ wọn sílẹ̀ ní ìdílé-ìdílé àti agbo ilé bàbá wọn. 30 Kí o forúkọ wọn sílẹ̀ láti ẹni ọgbọ̀n (30) ọdún sí àádọ́ta (50) ọdún, gbogbo ẹni tó wà lára àwọn tí a yàn pé kí wọ́n máa ṣiṣẹ́ nínú àgọ́ ìpàdé. 31 Àwọn ohun tí wọ́n á máa gbé+ tó jẹ mọ́ iṣẹ́ wọn nínú àgọ́ ìpàdé nìyí: àwọn férémù+ àgọ́ ìjọsìn, àwọn ọ̀pá ìdábùú+ rẹ̀, àwọn òpó+ rẹ̀, àwọn ìtẹ́lẹ̀ oníhò + rẹ̀; 32 àwọn òpó+ àgbàlá tó yí i ká, àwọn ìtẹ́lẹ̀ oníhò + wọn, àwọn èèkàn+ àgọ́ wọn àti àwọn okùn àgọ́ wọn pẹ̀lú gbogbo ohun èlò wọn àti gbogbo iṣẹ́ tó jẹ mọ́ nǹkan wọ̀nyí. Kí ẹ fi orúkọ yan ohun tí kálúku wọn á máa gbé. 33 Bí ìdílé àwọn ọmọ Mérárì+ á ṣe máa ṣiṣẹ́ nínú àgọ́ ìpàdé nìyí, kí Ítámárì ọmọ àlùfáà Áárónì+ máa darí wọn.”

34 Mósè àti Áárónì àti àwọn ìjòyè+ àpéjọ náà wá forúkọ àwọn ọmọ Kóhátì+ sílẹ̀ ní ìdílé-ìdílé àti agbo ilé bàbá wọn, 35 gbogbo àwọn tó jẹ́ ẹni ọgbọ̀n (30) ọdún sí àádọ́ta (50) ọdún, tí wọ́n wà lára àwọn tí a yàn pé kí wọ́n máa ṣiṣẹ́ nínú àgọ́ ìpàdé.+ 36 Gbogbo àwọn tí wọ́n forúkọ wọn sílẹ̀ ní ìdílé-ìdílé jẹ́ ẹgbẹ̀rún méjì ó lé ọgọ́rùn-ún méje àti àádọ́ta (2,750).+ 37 Èyí ni àwọn tí wọ́n forúkọ wọn sílẹ̀ nínú ìdílé àwọn ọmọ Kóhátì, gbogbo àwọn tó ń ṣiṣẹ́ nínú àgọ́ ìpàdé. Mósè àti Áárónì forúkọ wọn sílẹ̀ bí Jèhófà ṣe pa á láṣẹ nípasẹ̀ Mósè.+

38 Wọ́n forúkọ àwọn ọmọ Gẹ́ṣónì+ sílẹ̀ ní ìdílé-ìdílé àti agbo ilé bàbá wọn, 39 gbogbo àwọn tó jẹ́ ẹni ọgbọ̀n (30) ọdún sí àádọ́ta (50) ọdún, tí wọ́n wà lára àwọn tí a yàn pé kí wọ́n máa ṣiṣẹ́ nínú àgọ́ ìpàdé. 40 Gbogbo àwọn tí wọ́n forúkọ wọn sílẹ̀ ní ìdílé-ìdílé àti agbo ilé bàbá wọn jẹ́ ẹgbẹ̀rún méjì ó lé ọgọ́rùn-ún mẹ́fà àti ọgbọ̀n (2,630).+ 41 Bí wọ́n ṣe forúkọ ìdílé àwọn ọmọ Gẹ́ṣónì sílẹ̀ nìyí, gbogbo àwọn tó ń ṣiṣẹ́ nínú àgọ́ ìpàdé. Mósè àti Áárónì forúkọ wọn sílẹ̀ bí Jèhófà+ ṣe pa á láṣẹ.

42 Wọ́n forúkọ àwọn ọmọ Mérárì sílẹ̀ ní ìdílé-ìdílé àti agbo ilé bàbá wọn, 43 gbogbo àwọn tó jẹ́ ẹni ọgbọ̀n (30) ọdún sí àádọ́ta (50) ọdún, tí wọ́n wà lára àwọn tí a yàn pé kí wọ́n máa ṣiṣẹ́ nínú àgọ́ ìpàdé.+ 44 Gbogbo àwọn tí wọ́n forúkọ wọn sílẹ̀ ní ìdílé-ìdílé jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́ta ó lé igba (3,200).+ 45 Bí wọ́n ṣe forúkọ ìdílé àwọn ọmọ Mérárì sílẹ̀ nìyí, àwọn tí Mósè àti Áárónì forúkọ wọn sílẹ̀ bí Jèhófà ṣe pa á láṣẹ nípasẹ̀ Mósè.+

46 Mósè àti Áárónì àti àwọn ìjòyè Ísírẹ́lì forúkọ gbogbo àwọn ọmọ Léfì yìí sílẹ̀ ní ìdílé-ìdílé àti agbo ilé bàbá wọn; 47 wọ́n jẹ́ ẹni ọgbọ̀n (30) ọdún sí àádọ́ta (50) ọdún, gbogbo wọn ni a yàn láti máa ṣiṣẹ́, kí wọ́n sì máa gbé àwọn ẹrù tó jẹ mọ́ àgọ́ ìpàdé.+ 48 Gbogbo àwọn tí wọ́n forúkọ wọn sílẹ̀ jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́jọ ó lé ọgọ́rùn-ún márùn-ún àti ọgọ́rin (8,580).+ 49 Wọ́n forúkọ wọn sílẹ̀ bí Jèhófà ṣe pa á láṣẹ nípasẹ̀ Mósè, ní ìbámu pẹ̀lú iṣẹ́ tí wọ́n yàn fún kálukú àti ẹrù rẹ̀; wọ́n forúkọ wọn sílẹ̀ bí Jèhófà ṣe pa á láṣẹ fún Mósè.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́