ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Diutarónómì 4
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Diutarónómì

      • Wọ́n gbọ́dọ̀ jẹ́ onígbọràn (1-14)

        • Wọn ò gbọ́dọ̀ gbàgbé àwọn ohun tí Ọlọ́run ṣe (9)

      • Jèhófà fẹ́ kí wọ́n máa jọ́sìn òun nìkan (15-31)

      • Kò sí Ọlọ́run míì àfi Jèhófà (32-40)

      • Àwọn ìlú ààbò ní ìlà oòrùn Jọ́dánì (41-43)

      • Ó fún Ísírẹ́lì ní Òfin (44-49)

Diutarónómì 4:1

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Le 18:5

Diutarónómì 4:2

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Di 12:32; Owe 30:5, 6; Ifi 22:18, 19

Diutarónómì 4:3

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Nọ 25:5, 9; Sm 106:28; Ho 9:10; 1Kọ 10:7, 8

Diutarónómì 4:5

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Le 26:46; Nọ 30:16; 36:13; Di 6:1

Diutarónómì 4:6

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Ọb 2:3
  • +Sm 111:10
  • +Sm 119:98, 100
  • +1Ọb 4:34; 10:4-7; Da 1:19, 20

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àwọn Ìtẹ̀jáde Tá A Tọ́ka sí Nínú Ìwé Ìpàdé, 5/2021,

Diutarónómì 4:7

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 25:8; Le 26:12; Di 5:26; 2Sa 7:23

Diutarónómì 4:8

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Sm 147:19, 20

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    6/1/2002, ojú ìwé 14-15

    7/1/1992, ojú ìwé 11-12

Diutarónómì 4:9

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “kí o sì máa ṣọ́ ọkàn rẹ dáadáa.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 18:19; Di 6:6, 7

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    6/1/2006, ojú ìwé 29-30

    Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run, ojú ìwé 20

Diutarónómì 4:10

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 19:9
  • +Ẹk 20:20; Di 5:29
  • +Owe 22:6; Ef 6:4

Diutarónómì 4:11

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “títí dé àárín àwọn ọ̀run.”

  • *

    Tàbí “àwọsánmà.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 19:18; Heb 12:18, 19

Diutarónómì 4:12

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Di 9:10
  • +Ais 40:18; Jo 1:18; 4:24
  • +Ẹk 20:22

Diutarónómì 4:13

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “Ọ̀rọ̀ Mẹ́wàá.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 19:5; Di 5:2; 9:9; Heb 9:19, 20
  • +Ẹk 20:1; 34:28; Di 10:4
  • +Ẹk 24:12; 31:18; 32:19; 34:1

Diutarónómì 4:15

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ẹ ṣọ́ ọkàn yín gidigidi.”

Diutarónómì 4:16

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 20:4; Di 27:15; Ais 40:18; Iṣe 17:29; 1Kọ 10:14

Diutarónómì 4:17

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Di 5:8; Ro 1:22, 23

Diutarónómì 4:18

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Sa 5:4

Diutarónómì 4:19

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Di 17:2, 3; 2Ọb 17:16; Isk 8:16

Diutarónómì 4:20

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ogún rẹ̀.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 19:5

Diutarónómì 4:21

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Sm 106:32
  • +Nọ 20:12; Di 31:1, 2

Diutarónómì 4:22

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Di 3:27

Diutarónómì 4:23

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 24:3
  • +Ẹk 20:4

Diutarónómì 4:24

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 24:17; Di 9:3; Heb 12:29
  • +Ẹk 20:5; 34:14; Nọ 25:11; Lk 10:27

Diutarónómì 4:25

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ond 18:30; 2Ọb 21:1, 7
  • +2Ọb 17:16, 17

Diutarónómì 4:26

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Le 18:24, 28; 26:27, 32

Diutarónómì 4:27

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Di 28:64; Ne 1:8
  • +Di 28:62

Diutarónómì 4:28

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Di 28:15, 36; Jer 16:13; Isk 20:39

Diutarónómì 4:29

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀, “Ọkàn.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Kr 15:4, 15
  • +Di 30:1-3, 8-10; 1Ọb 8:48, 49; Jer 29:13; Joẹ 2:12

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àwọn Ìtẹ̀jáde Tá A Tọ́ka sí Nínú Ìwé Ìpàdé, 7/2021,

Diutarónómì 4:30

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Kr 33:13; Ne 1:9

Diutarónómì 4:31

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 34:6; Di 30:3; 2Kr 30:9; Ne 9:31; Ais 54:7; 55:7
  • +Le 26:42

Diutarónómì 4:32

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Sm 44:1

Diutarónómì 4:33

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Di 5:26

Diutarónómì 4:34

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ìgbẹ́jọ́.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 7:3
  • +Ẹk 15:3
  • +Ẹk 13:3
  • +Di 26:8; Sm 78:43-51

Diutarónómì 4:35

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 6:7
  • +Ẹk 15:11; Di 32:39; 1Sa 2:2; Ais 45:18; Mk 12:32

Diutarónómì 4:36

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 19:18; 20:22

Diutarónómì 4:37

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “èso.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Di 10:15; Sm 105:6

Diutarónómì 4:38

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 23:28; Di 7:1; 9:1; Joṣ 3:10

Diutarónómì 4:39

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Kr 20:6
  • +Ais 44:6

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!, ẹ̀kọ́ 4

Diutarónómì 4:40

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 48:3, 4

Diutarónómì 4:41

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Nọ 35:14

Diutarónómì 4:42

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Nọ 35:22-24
  • +Nọ 35:11, 25; Di 19:4, 5

Diutarónómì 4:43

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “òkè tí orí rẹ̀ rí pẹrẹsẹ.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Joṣ 21:8, 36
  • +Joṣ 21:8, 38
  • +Joṣ 21:27
  • +Joṣ 20:8, 9

Diutarónómì 4:44

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Di 17:18; 27:2, 3; Ga 3:24

Diutarónómì 4:45

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Le 26:46; Di 4:1

Diutarónómì 4:46

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Di 1:5; 3:29
  • +Nọ 21:26
  • +Nọ 21:23, 24

Diutarónómì 4:47

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Nọ 21:33; Di 3:4

Diutarónómì 4:48

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Di 2:36; 3:12
  • +Di 3:8, 9

Diutarónómì 4:49

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ìyẹn, Òkun Iyọ̀ tàbí Òkun Òkú.

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Di 3:16, 17; 34:1

Àwọn míì

Diu. 4:1Le 18:5
Diu. 4:2Di 12:32; Owe 30:5, 6; Ifi 22:18, 19
Diu. 4:3Nọ 25:5, 9; Sm 106:28; Ho 9:10; 1Kọ 10:7, 8
Diu. 4:5Le 26:46; Nọ 30:16; 36:13; Di 6:1
Diu. 4:61Ọb 2:3
Diu. 4:6Sm 111:10
Diu. 4:6Sm 119:98, 100
Diu. 4:61Ọb 4:34; 10:4-7; Da 1:19, 20
Diu. 4:7Ẹk 25:8; Le 26:12; Di 5:26; 2Sa 7:23
Diu. 4:8Sm 147:19, 20
Diu. 4:9Jẹ 18:19; Di 6:6, 7
Diu. 4:10Ẹk 19:9
Diu. 4:10Ẹk 20:20; Di 5:29
Diu. 4:10Owe 22:6; Ef 6:4
Diu. 4:11Ẹk 19:18; Heb 12:18, 19
Diu. 4:12Di 9:10
Diu. 4:12Ais 40:18; Jo 1:18; 4:24
Diu. 4:12Ẹk 20:22
Diu. 4:13Ẹk 19:5; Di 5:2; 9:9; Heb 9:19, 20
Diu. 4:13Ẹk 20:1; 34:28; Di 10:4
Diu. 4:13Ẹk 24:12; 31:18; 32:19; 34:1
Diu. 4:16Ẹk 20:4; Di 27:15; Ais 40:18; Iṣe 17:29; 1Kọ 10:14
Diu. 4:17Di 5:8; Ro 1:22, 23
Diu. 4:181Sa 5:4
Diu. 4:19Di 17:2, 3; 2Ọb 17:16; Isk 8:16
Diu. 4:20Ẹk 19:5
Diu. 4:21Sm 106:32
Diu. 4:21Nọ 20:12; Di 31:1, 2
Diu. 4:22Di 3:27
Diu. 4:23Ẹk 24:3
Diu. 4:23Ẹk 20:4
Diu. 4:24Ẹk 24:17; Di 9:3; Heb 12:29
Diu. 4:24Ẹk 20:5; 34:14; Nọ 25:11; Lk 10:27
Diu. 4:25Ond 18:30; 2Ọb 21:1, 7
Diu. 4:252Ọb 17:16, 17
Diu. 4:26Le 18:24, 28; 26:27, 32
Diu. 4:27Di 28:64; Ne 1:8
Diu. 4:27Di 28:62
Diu. 4:28Di 28:15, 36; Jer 16:13; Isk 20:39
Diu. 4:292Kr 15:4, 15
Diu. 4:29Di 30:1-3, 8-10; 1Ọb 8:48, 49; Jer 29:13; Joẹ 2:12
Diu. 4:302Kr 33:13; Ne 1:9
Diu. 4:31Ẹk 34:6; Di 30:3; 2Kr 30:9; Ne 9:31; Ais 54:7; 55:7
Diu. 4:31Le 26:42
Diu. 4:32Sm 44:1
Diu. 4:33Di 5:26
Diu. 4:34Ẹk 7:3
Diu. 4:34Ẹk 15:3
Diu. 4:34Ẹk 13:3
Diu. 4:34Di 26:8; Sm 78:43-51
Diu. 4:35Ẹk 6:7
Diu. 4:35Ẹk 15:11; Di 32:39; 1Sa 2:2; Ais 45:18; Mk 12:32
Diu. 4:36Ẹk 19:18; 20:22
Diu. 4:37Di 10:15; Sm 105:6
Diu. 4:38Ẹk 23:28; Di 7:1; 9:1; Joṣ 3:10
Diu. 4:392Kr 20:6
Diu. 4:39Ais 44:6
Diu. 4:40Jẹ 48:3, 4
Diu. 4:41Nọ 35:14
Diu. 4:42Nọ 35:22-24
Diu. 4:42Nọ 35:11, 25; Di 19:4, 5
Diu. 4:43Joṣ 21:8, 36
Diu. 4:43Joṣ 21:8, 38
Diu. 4:43Joṣ 21:27
Diu. 4:43Joṣ 20:8, 9
Diu. 4:44Di 17:18; 27:2, 3; Ga 3:24
Diu. 4:45Le 26:46; Di 4:1
Diu. 4:46Di 1:5; 3:29
Diu. 4:46Nọ 21:26
Diu. 4:46Nọ 21:23, 24
Diu. 4:47Nọ 21:33; Di 3:4
Diu. 4:48Di 2:36; 3:12
Diu. 4:48Di 3:8, 9
Diu. 4:49Di 3:16, 17; 34:1
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
  • 1
  • 2
  • 3
  • 4
  • 5
  • 6
  • 7
  • 8
  • 9
  • 10
  • 11
  • 12
  • 13
  • 14
  • 15
  • 16
  • 17
  • 18
  • 19
  • 20
  • 21
  • 22
  • 23
  • 24
  • 25
  • 26
  • 27
  • 28
  • 29
  • 30
  • 31
  • 32
  • 33
  • 34
  • 35
  • 36
  • 37
  • 38
  • 39
  • 40
  • 41
  • 42
  • 43
  • 44
  • 45
  • 46
  • 47
  • 48
  • 49
Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
Diutarónómì 4:1-49

Diutarónómì

4 “Ní báyìí, ẹ̀yin ọmọ Ísírẹ́lì, ẹ fetí sí àwọn ìlànà àti àwọn ìdájọ́ tí mò ń kọ́ yín láti pa mọ́, kí ẹ lè máa wà láàyè,+ kí ẹ lè wọ ilẹ̀ tí Jèhófà Ọlọ́run àwọn baba ńlá yín máa fún yín, kí ẹ sì gbà á. 2 Ẹ ò gbọ́dọ̀ fi kún ọ̀rọ̀ tí mò ń pa láṣẹ fún yín, ẹ ò sì gbọ́dọ̀ yọ kúrò lára rẹ̀,+ kí ẹ lè máa tẹ̀ lé àwọn àṣẹ Jèhófà Ọlọ́run yín tí mò ń pa láṣẹ fún yín.

3 “Ẹ ti fi ojú ara yín rí ohun tí Jèhófà ṣe nínú ọ̀rọ̀ Báálì Péórì; gbogbo ọkùnrin tó tọ Báálì Péórì+ lẹ́yìn ni Jèhófà Ọlọ́run yín pa run kúrò láàárín yín. 4 Àmọ́ gbogbo ẹ̀yin tí ẹ rọ̀ mọ́ Jèhófà Ọlọ́run yín lẹ wà láàyè lónìí. 5 Ẹ wò ó, mo ti kọ́ yín ní àwọn ìlànà àti àwọn ìdájọ́,+ bí Jèhófà Ọlọ́run mi ṣe pa á láṣẹ fún mi gẹ́lẹ́, kí ẹ lè máa pa wọ́n mọ́ ní ilẹ̀ tí ẹ máa gbà. 6 Kí ẹ rí i pé ẹ̀ ń pa wọ́n mọ́,+ torí èyí máa fi hàn pé ẹ jẹ́ ọlọ́gbọ́n+ àti olóye+ lójú àwọn èèyàn tó máa gbọ́ nípa gbogbo ìlànà yìí, wọ́n á sì sọ pé, ‘Ó dájú pé ọlọ́gbọ́n àti olóye ni àwọn èèyàn orílẹ̀-èdè ńlá yìí.’+ 7 Orílẹ̀-èdè ńlá wo ni àwọn ọlọ́run rẹ̀ sún mọ́ ọn bíi ti Jèhófà Ọlọ́run wa nígbàkigbà tí a bá ké pè é?+ 8 Orílẹ̀-èdè ńlá wo ló sì ní àwọn ìlànà òdodo àti àwọn ìdájọ́ bíi ti gbogbo Òfin yìí tí mò ń fi sí iwájú yín lónìí?+

9 “Ṣáà máa kíyè sára, kí o sì máa ṣọ́ra gan-an,* kí o má bàa gbàgbé àwọn ohun tí o fi ojú rẹ rí, kí wọ́n má bàa kúrò lọ́kàn rẹ ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ. Kí o sì tún jẹ́ kí àwọn ọmọ rẹ àti àwọn ọmọ ọmọ rẹ mọ̀ nípa wọn.+ 10 Ní ọjọ́ tí o dúró níwájú Jèhófà Ọlọ́run rẹ ní Hórébù, Jèhófà sọ fún mi pé, ‘Pe àwọn èèyàn náà jọ sọ́dọ̀ mi kí n lè mú kí wọ́n gbọ́ àwọn ọ̀rọ̀ mi,+ kí wọ́n lè kọ́ láti máa bẹ̀rù mi+ ní gbogbo ọjọ́ tí wọ́n á fi wà láàyè lórí ilẹ̀, kí wọ́n sì lè kọ́ àwọn ọmọ wọn.’+

11 “Ẹ wá sún mọ́ tòsí òkè náà, ẹ sì dúró sí ìsàlẹ̀ rẹ̀, òkè náà sì ń yọ iná títí dé ọ̀run;* òkùnkùn ṣú, ìkùukùu* yọ, ojú ọjọ́ sì ṣú dùdù.+ 12 Jèhófà wá bẹ̀rẹ̀ sí í bá yín sọ̀rọ̀ látinú iná náà.+ Ẹ̀ ń gbọ́ tí ẹnì kan ń sọ̀rọ̀, àmọ́ ẹ ò rí ẹnì kankan,+ ohùn nìkan lẹ̀ ń gbọ́.+ 13 Ó sì kéde májẹ̀mú rẹ̀ fún yín,+ èyí tó pa láṣẹ fún yín pé kí ẹ máa pa mọ́, ìyẹn Òfin Mẹ́wàá.*+ Lẹ́yìn náà, ó kọ ọ́ sórí wàláà òkúta méjì.+ 14 Nígbà yẹn, Jèhófà pàṣẹ fún mi pé kí n kọ́ yín ní àwọn ìlànà àti àwọn ìdájọ́ tí ẹ ó máa pa mọ́ ní ilẹ̀ tí ẹ fẹ́ lọ gbà.

15 “Torí náà, ẹ ṣọ́ra gidigidi,* torí pé ẹ ò rí ẹnikẹ́ni lọ́jọ́ tí Jèhófà bá yín sọ̀rọ̀ ní Hórébù láti àárín iná náà, 16 kí ẹ má bàa hùwàkiwà nípa gbígbẹ́ ère èyíkéyìí tó jọ ohunkóhun fún ara yín, ohun tó rí bí akọ tàbí abo,+ 17 ohun tó rí bí ẹranko èyíkéyìí ní ayé, bí ẹyẹ tó ń fò lójú ọ̀run,+ 18 bí ohunkóhun tó ń rákò lórí ilẹ̀ tàbí tó rí bí ẹja èyíkéyìí nínú omi lábẹ́ ilẹ̀.+ 19 Tí o bá wá yíjú sókè wo ọ̀run, tí o sì rí oòrùn, òṣùpá àti àwọn ìràwọ̀, gbogbo ọmọ ogun ọ̀run, o ò gbọ́dọ̀ jẹ́ kí ọkàn rẹ fà sí wọn débi pé o máa forí balẹ̀ fún wọn, tí o sì máa sìn wọ́n.+ Gbogbo èèyàn lábẹ́ ọ̀run ni Jèhófà Ọlọ́run rẹ fi wọ́n fún. 20 Àmọ́ ẹ̀yin ni Jèhófà mú jáde nínú iná ìléru tí wọ́n ti ń yọ́ irin, kúrò nílẹ̀ Íjíbítì, kí ẹ lè di ohun ìní rẹ̀*+ bí ẹ ṣe jẹ́ lónìí.

21 “Jèhófà bínú sí mi torí yín,+ ó sì búra pé mi ò ní sọdá Jọ́dánì, mi ò sì ní wọ ilẹ̀ dáradára tí Jèhófà Ọlọ́run yín fẹ́ fún yín láti jogún.+ 22 Ilẹ̀ yìí ni màá kú sí; mi ò ní sọdá Jọ́dánì,+ ṣùgbọ́n ẹ̀yin máa sọdá, ẹ sì máa gba ilẹ̀ dáradára náà. 23 Ẹ ṣọ́ra kí ẹ má bàa gbàgbé májẹ̀mú tí Jèhófà Ọlọ́run yín bá yín dá,+ ẹ má sì gbẹ́ ère fún ara yín, ohun tó rí bí ohunkóhun tí Jèhófà Ọlọ́run yín kà léèwọ̀ fún yín.+ 24 Torí iná tó ń jóni run ni Jèhófà Ọlọ́run yín,+ Ọlọ́run tó fẹ́ kí ẹ máa jọ́sìn òun nìkan ṣoṣo.+

25 “Tí ẹ bá bí àwọn ọmọ, tí ẹ sì ní àwọn ọmọ ọmọ, tí ẹ sì ti pẹ́ ní ilẹ̀ náà, àmọ́ tí ẹ wá ṣe ohun tó lè fa ìparun, tí ẹ gbẹ́ ère+ èyíkéyìí, tí ẹ sì ṣe ohun tó burú lójú Jèhófà Ọlọ́run yín láti mú un bínú,+ 26 mo fi ọ̀run àti ayé ṣe ẹlẹ́rìí ta kò yín lónìí, pé ó dájú pé kíákíá lẹ máa pa run ní ilẹ̀ tí ẹ̀ ń sọdá Jọ́dánì láti lọ gbà. Ẹ ò ní pẹ́ níbẹ̀, ṣe lẹ máa pa run pátápátá.+ 27 Jèhófà máa tú yín ká sáàárín àwọn èèyàn,+ díẹ̀ nínú yín ló sì máa ṣẹ́ kù+ láàárín àwọn orílẹ̀-èdè tí Jèhófà máa lé yín lọ. 28 Àwọn ọlọ́run tí wọ́n fi igi àti òkúta ṣe lẹ máa sìn níbẹ̀, èyí tí àwọn èèyàn fi ọwọ́ ṣe,+ àwọn ọlọ́run tí kò lè ríran, tí kò lè gbọ́ràn, tí kò lè jẹun, tí kò sì lè gbóòórùn.

29 “Tí ẹ bá wá Jèhófà Ọlọ́run yín níbẹ̀, ó dájú pé ẹ máa rí i+ tí ẹ bá fi gbogbo ọkàn yín àti gbogbo ara* yín wá a.+ 30 Tí wàhálà tó le gan-an bá dé bá ọ, tí gbogbo nǹkan yìí sì wá ṣẹlẹ̀ sí ọ, wàá pa dà sọ́dọ̀ Jèhófà Ọlọ́run rẹ, wàá sì fetí sí ohùn rẹ̀.+ 31 Torí Ọlọ́run aláàánú ni Jèhófà Ọlọ́run rẹ.+ Kò ní pa ọ́ tì, kò ní pa ọ́ run, kò sì ní gbàgbé májẹ̀mú tó bá àwọn baba ńlá rẹ dá.+

32 “Béèrè báyìí nípa ìgbà àtijọ́, ṣáájú ìgbà tìẹ, láti ọjọ́ tí Ọlọ́run ti dá èèyàn sí ayé; wádìí láti ìpẹ̀kun kan ọ̀run sí ìpẹ̀kun kejì. Ṣé irú nǹkan àgbàyanu bẹ́ẹ̀ ti ṣẹlẹ̀ rí àbí ẹ ti gbọ́ ohunkóhun tó jọ ọ́ rí?+ 33 Ǹjẹ́ àwọn èèyàn míì gbọ́ ohùn Ọlọ́run tó ń sọ̀rọ̀ látinú iná bí ẹ ṣe gbọ́ ọ, tí ẹ ò sì kú?+ 34 Àbí Ọlọ́run ti gbìyànjú láti mú orílẹ̀-èdè kan fún ara rẹ̀ látinú orílẹ̀-èdè míì pẹ̀lú àwọn ìdájọ́,* àmì, iṣẹ́ ìyanu,+ ogun,+ pẹ̀lú ọwọ́ agbára,+ apá tó nà jáde, tó sì ṣe àwọn nǹkan tó ń bani lẹ́rù,+ bí Jèhófà Ọlọ́run yín ṣe ṣe fún yín ní Íjíbítì níṣojú yín? 35 Ẹ̀yin fúnra yín ti rí nǹkan wọ̀nyí kí ẹ lè mọ̀ pé Jèhófà ni Ọlọ́run tòótọ́;+ kò sí ẹlòmíì àfi òun nìkan.+ 36 Ó mú kí o gbọ́ ohùn rẹ̀ láti ọ̀run, kó lè tọ́ ọ sọ́nà, ó mú kí o rí iná ńlá rẹ̀ ní ayé, o sì gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀ látinú iná.+

37 “Torí pé ó nífẹ̀ẹ́ àwọn baba ńlá rẹ, ó sì yan àtọmọdọ́mọ* wọn lẹ́yìn wọn,+ ó fi agbára ńlá rẹ̀ mú ọ kúrò ní Íjíbítì pẹ̀lú ojú rẹ̀ lára rẹ. 38 Ó lé àwọn orílẹ̀-èdè tó tóbi, tí wọ́n sì lágbára jù ọ́ lọ kúrò níwájú rẹ, kó lè mú ọ wọlé, kó sì fún ọ ní ilẹ̀ wọn kí o lè jogún rẹ̀, bó ṣe rí lónìí.+ 39 Torí náà, kí o mọ̀ lónìí, kí o sì fi sọ́kàn pé Jèhófà ni Ọlọ́run tòótọ́ lókè ọ̀run àti lórí ilẹ̀ ayé.+ Kò sí ẹlòmíì.+ 40 Kí o máa tẹ̀ lé àwọn ìlànà àti àwọn àṣẹ rẹ̀, èyí tí mò ń pa láṣẹ fún ọ lónìí, kí nǹkan lè máa lọ dáadáa fún ìwọ àti àwọn ọmọ rẹ lẹ́yìn rẹ, kí o lè pẹ́ lórí ilẹ̀ tí Jèhófà Ọlọ́run rẹ máa fún ọ.”+

41 Nígbà yẹn, Mósè ya ìlú mẹ́ta sọ́tọ̀ ní apá ìlà oòrùn Jọ́dánì.+ 42 Tí apààyàn èyíkéyìí bá ṣèèṣì pa ọmọnìkejì rẹ̀, tí kì í sì í ṣe pé ó kórìíra rẹ̀ tẹ́lẹ̀,+ kó sá lọ sí ọ̀kan lára àwọn ìlú yìí, kí wọ́n má bàa pa á.+ 43 Àwọn ìlú náà ni Bésérì+ ní aginjù, lórí ilẹ̀ tó tẹ́jú,* fún àwọn ọmọ Rúbẹ́nì, Rámótì+ ní Gílíádì fún àwọn ọmọ Gádì àti Gólánì+ ní Báṣánì fún àwọn ọmọ Mánásè.+

44 Èyí ni Òfin+ tí Mósè fi lélẹ̀ níwájú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì. 45 Èyí ni àwọn ìrántí, àwọn ìlànà àti àwọn ìdájọ́ tí Mósè fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lẹ́yìn tí wọ́n kúrò ní Íjíbítì,+ 46 ní agbègbè Jọ́dánì, ní àfonífojì tó dojú kọ Bẹti-péórì,+ ní ilẹ̀ Síhónì ọba àwọn Ámórì, tó ń gbé ní Hẹ́ṣíbónì,+ ẹni tí Mósè àti àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣẹ́gun lẹ́yìn tí wọ́n kúrò ní Íjíbítì.+ 47 Wọ́n sì gba ilẹ̀ rẹ̀ àti ilẹ̀ Ógù+ ọba Báṣánì, àwọn ọba Ámórì méjèèjì, tí wọ́n wà ní agbègbè tó wà ní ìlà oòrùn Jọ́dánì, 48 láti Áróérì,+ èyí tó wà létí Àfonífojì Áánónì, títí dé Òkè Síónì, ìyẹn Hámónì,+ 49 àti gbogbo Árábà, ní agbègbè tó wà ní ìlà oòrùn Jọ́dánì, títí lọ dé Òkun Árábà,* ní ìsàlẹ̀ àwọn gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ Písígà.+

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́