ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Léfítíkù 26
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Léfítíkù

      • Ẹ má ṣe bọ̀rìṣà (1, 2)

      • Ìbùkún tí wọ́n máa rí tí wọ́n bá ṣègbọràn (3-13)

      • Ìyà tí wọ́n máa jẹ tí wọ́n bá ṣàìgbọràn (14-46)

Léfítíkù 26:1

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 20:4; Le 19:4; Iṣe 17:29; 1Kọ 8:4
  • +Di 5:8
  • +Nọ 33:52
  • +Da 3:18; 1Kọ 10:14

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!, ẹ̀kọ́ 19

Léfítíkù 26:2

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “bẹ̀rù.”

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àwọn Ìtẹ̀jáde Tá A Tọ́ka sí Nínú Ìwé Ìpàdé, 1/2021,

Léfítíkù 26:3

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Di 11:13-15; Onw 12:13

Léfítíkù 26:4

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Di 28:12; Ais 30:23; Isk 34:26; Joẹ 2:23
  • +Sm 67:6; 85:12

Léfítíkù 26:5

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Le 25:18

Léfítíkù 26:6

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Kr 22:9; Sm 29:11; Hag 2:9
  • +Mik 4:4

Léfítíkù 26:8

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Di 28:7; Joṣ 23:10; Ond 7:15, 16; 15:15, 16; 1Kr 11:20

Léfítíkù 26:9

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “yíjú.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Di 28:4
  • +Ẹk 6:4

Léfítíkù 26:11

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “ọkàn mi.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 25:8; Isk 37:26; Ifi 21:3

Léfítíkù 26:12

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Di 23:14
  • +Ẹk 6:7; 2Kọ 6:16

Léfítíkù 26:13

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “rìn pẹ̀lú orí yín lókè.”

Léfítíkù 26:14

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Di 28:15

Léfítíkù 26:15

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ọkàn yín.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Ọb 17:15
  • +Ẹk 24:7; Di 31:16; Heb 8:9

Léfítíkù 26:16

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ọkàn yín.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Di 28:22, 33; Ond 6:3

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àwọn Ìtẹ̀jáde Tá A Tọ́ka sí Nínú Ìwé Ìpàdé, 1/2021,

Léfítíkù 26:17

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Di 28:15, 25; Ond 2:14; 1Sa 4:10
  • +Sm 106:41; Ida 1:5
  • +Le 26:36

Léfítíkù 26:19

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Di 11:17; 1Ọb 17:1

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    5/15/2004, ojú ìwé 24

Léfítíkù 26:20

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jer 12:13; Hag 1:6, 10

Léfítíkù 26:22

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Di 32:24; Jer 15:3
  • +Isk 5:17
  • +Ond 5:6; Ais 33:8; Sek 7:14

Léfítíkù 26:23

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ais 1:16; Jer 2:30; 5:3

Léfítíkù 26:25

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 24:7
  • +Di 28:21; Jer 24:10; Emọ 4:10
  • +Ond 2:14; 1Sa 4:10

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àwọn Ìtẹ̀jáde Tá A Tọ́ka sí Nínú Ìwé Ìpàdé, 1/2021,

Léfítíkù 26:26

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “ọ̀pá.” Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ àwọn ọ̀pá tí wọ́n fi ń tọ́jú búrẹ́dì.

  • *

    Tàbí “oúnjẹ.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Isk 5:16
  • +Isk 4:16
  • +Ais 9:20; Mik 6:14; Hag 1:6

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    5/15/2004, ojú ìwé 24

Léfítíkù 26:28

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jer 21:5

Léfítíkù 26:29

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Di 28:53; 2Ọb 6:29; Jer 19:9; Ida 4:10; Isk 5:10

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Jeremáyà, ojú ìwé 154-155

Léfítíkù 26:30

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ó ṣeé ṣe kí ọ̀rọ̀ Hébérù yìí ní í ṣe pẹ̀lú ọ̀rọ̀ tí wọ́n ń lò fún “ìgbẹ́,” wọ́n sì máa ń lò ó fún ohun tí wọ́n bá kórìíra.

  • *

    Tàbí “ọkàn mi.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Kr 34:3; Ais 27:9
  • +1Ọb 13:2; 2Ọb 23:8, 20; Isk 6:5
  • +Sm 78:58, 59

Léfítíkù 26:31

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “tó tuni lójú.” Ní Héb., “atura.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Ọb 25:9, 10; 2Kr 36:17; Ne 2:3; Ais 1:7; Jer 4:7

Léfítíkù 26:32

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jer 9:11
  • +Di 28:37; 29:22-24; Jer 18:16; Ida 2:15; Isk 5:15

Léfítíkù 26:33

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Sm 44:11
  • +Jer 9:16; Isk 12:14
  • +Sek 7:14

Léfítíkù 26:34

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “pa sábáàtì mọ́.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Kr 36:20, 21

Léfítíkù 26:36

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ais 24:6
  • +Le 26:17; Ais 30:17

Léfítíkù 26:37

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Joṣ 7:12; Ond 2:14; Jer 37:10

Léfítíkù 26:38

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Di 4:27; 28:48; Jer 42:17

Léfítíkù 26:39

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Di 28:65
  • +Ẹk 20:5; Nọ 14:18

Léfítíkù 26:40

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Ọb 8:33; Ne 9:2; Isk 6:9; Da 9:5
  • +Isk 36:31

Léfítíkù 26:41

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ọkàn wọn tó le;” “tí wọn ò dá bí ẹni dá adọ̀dọ́.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Le 26:24
  • +1Ọb 8:47; 2Kr 36:20
  • +Di 30:6; Jer 4:4; Iṣe 7:51

Léfítíkù 26:42

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 28:13
  • +Jẹ 26:3
  • +Jẹ 12:7; Di 4:31; Sm 106:45

Léfítíkù 26:43

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ọkàn wọn.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Le 26:34; 2Kr 36:20, 21
  • +2Ọb 17:15

Léfítíkù 26:44

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Di 4:31; 2Ọb 13:23; Ne 9:31
  • +Di 4:13; Jer 14:21

Léfítíkù 26:45

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 24:3, 8; Di 9:9
  • +Isk 20:9

Léfítíkù 26:46

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Le 27:34; Di 6:1

Àwọn míì

Léf. 26:1Ẹk 20:4; Le 19:4; Iṣe 17:29; 1Kọ 8:4
Léf. 26:1Di 5:8
Léf. 26:1Nọ 33:52
Léf. 26:1Da 3:18; 1Kọ 10:14
Léf. 26:3Di 11:13-15; Onw 12:13
Léf. 26:4Di 28:12; Ais 30:23; Isk 34:26; Joẹ 2:23
Léf. 26:4Sm 67:6; 85:12
Léf. 26:5Le 25:18
Léf. 26:61Kr 22:9; Sm 29:11; Hag 2:9
Léf. 26:6Mik 4:4
Léf. 26:8Di 28:7; Joṣ 23:10; Ond 7:15, 16; 15:15, 16; 1Kr 11:20
Léf. 26:9Di 28:4
Léf. 26:9Ẹk 6:4
Léf. 26:11Ẹk 25:8; Isk 37:26; Ifi 21:3
Léf. 26:12Di 23:14
Léf. 26:12Ẹk 6:7; 2Kọ 6:16
Léf. 26:14Di 28:15
Léf. 26:152Ọb 17:15
Léf. 26:15Ẹk 24:7; Di 31:16; Heb 8:9
Léf. 26:16Di 28:22, 33; Ond 6:3
Léf. 26:17Di 28:15, 25; Ond 2:14; 1Sa 4:10
Léf. 26:17Sm 106:41; Ida 1:5
Léf. 26:17Le 26:36
Léf. 26:19Di 11:17; 1Ọb 17:1
Léf. 26:20Jer 12:13; Hag 1:6, 10
Léf. 26:22Di 32:24; Jer 15:3
Léf. 26:22Isk 5:17
Léf. 26:22Ond 5:6; Ais 33:8; Sek 7:14
Léf. 26:23Ais 1:16; Jer 2:30; 5:3
Léf. 26:25Ẹk 24:7
Léf. 26:25Di 28:21; Jer 24:10; Emọ 4:10
Léf. 26:25Ond 2:14; 1Sa 4:10
Léf. 26:26Isk 5:16
Léf. 26:26Isk 4:16
Léf. 26:26Ais 9:20; Mik 6:14; Hag 1:6
Léf. 26:28Jer 21:5
Léf. 26:29Di 28:53; 2Ọb 6:29; Jer 19:9; Ida 4:10; Isk 5:10
Léf. 26:302Kr 34:3; Ais 27:9
Léf. 26:301Ọb 13:2; 2Ọb 23:8, 20; Isk 6:5
Léf. 26:30Sm 78:58, 59
Léf. 26:312Ọb 25:9, 10; 2Kr 36:17; Ne 2:3; Ais 1:7; Jer 4:7
Léf. 26:32Jer 9:11
Léf. 26:32Di 28:37; 29:22-24; Jer 18:16; Ida 2:15; Isk 5:15
Léf. 26:33Sm 44:11
Léf. 26:33Jer 9:16; Isk 12:14
Léf. 26:33Sek 7:14
Léf. 26:342Kr 36:20, 21
Léf. 26:36Ais 24:6
Léf. 26:36Le 26:17; Ais 30:17
Léf. 26:37Joṣ 7:12; Ond 2:14; Jer 37:10
Léf. 26:38Di 4:27; 28:48; Jer 42:17
Léf. 26:39Di 28:65
Léf. 26:39Ẹk 20:5; Nọ 14:18
Léf. 26:401Ọb 8:33; Ne 9:2; Isk 6:9; Da 9:5
Léf. 26:40Isk 36:31
Léf. 26:41Le 26:24
Léf. 26:411Ọb 8:47; 2Kr 36:20
Léf. 26:41Di 30:6; Jer 4:4; Iṣe 7:51
Léf. 26:42Jẹ 28:13
Léf. 26:42Jẹ 26:3
Léf. 26:42Jẹ 12:7; Di 4:31; Sm 106:45
Léf. 26:43Le 26:34; 2Kr 36:20, 21
Léf. 26:432Ọb 17:15
Léf. 26:44Di 4:31; 2Ọb 13:23; Ne 9:31
Léf. 26:44Di 4:13; Jer 14:21
Léf. 26:45Ẹk 24:3, 8; Di 9:9
Léf. 26:45Isk 20:9
Léf. 26:46Le 27:34; Di 6:1
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
  • 1
  • 2
  • 3
  • 4
  • 5
  • 6
  • 7
  • 8
  • 9
  • 10
  • 11
  • 12
  • 13
  • 14
  • 15
  • 16
  • 17
  • 18
  • 19
  • 20
  • 21
  • 22
  • 23
  • 24
  • 25
  • 26
  • 27
  • 28
  • 29
  • 30
  • 31
  • 32
  • 33
  • 34
  • 35
  • 36
  • 37
  • 38
  • 39
  • 40
  • 41
  • 42
  • 43
  • 44
  • 45
  • 46
Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
Léfítíkù 26:1-46

Léfítíkù

26 “‘Ẹ ò gbọ́dọ̀ ṣe àwọn ọlọ́run tí kò ní láárí fún ara yín,+ ẹ ò gbọ́dọ̀ ṣe ère gbígbẹ́+ tàbí ọwọ̀n òrìṣà fún ara yín, ẹ ò sì gbọ́dọ̀ gbé ère òkúta+ tí ẹ gbẹ́ sí ilẹ̀ yín láti forí balẹ̀ fún un;+ torí èmi ni Jèhófà Ọlọ́run yín. 2 Kí ẹ máa pa àwọn sábáàtì mi mọ́, kí ẹ sì máa bọ̀wọ̀ fún* ibi mímọ́ mi. Èmi ni Jèhófà.

3 “‘Tí ẹ bá ń tẹ̀ lé àwọn òfin mi, tí ẹ̀ ń pa àwọn àṣẹ mi mọ́, tí ẹ sì ń ṣe wọ́n,+ 4 èmi yóò rọ ọ̀wààrà òjò fún yín ní àkókò tó yẹ,+ ilẹ̀ yóò mú èso jáde,+ àwọn igi oko yóò sì so èso. 5 Ẹ ó máa pakà títí di ìgbà tí ẹ máa kórè èso àjàrà, ẹ ó sì máa kórè èso àjàrà títí di ìgbà tí ẹ máa fúnrúgbìn; ẹ ó jẹun ní àjẹyó, ẹ ó sì máa gbé láìséwu ní ilẹ̀ yín.+ 6 Màá mú kí àlàáfíà wà ní ilẹ̀ náà,+ ẹ ó sì dùbúlẹ̀ láìsí ẹni tó máa dẹ́rù bà yín;+ màá mú àwọn ẹranko burúkú kúrò ní ilẹ̀ náà, idà ogun ò sì ní kọjá ní ilẹ̀ yín. 7 Ó dájú pé ẹ máa lé àwọn ọ̀tá yín, ẹ ó sì fi idà ṣẹ́gun wọn. 8 Ẹ̀yin márùn-ún yóò lé ọgọ́rùn-ún (100), ẹ̀yin ọgọ́rùn-ún (100) yóò lé ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá (10,000), ẹ ó sì fi idà ṣẹ́gun àwọn ọ̀tá yín.+

9 “‘Màá ṣojúure* sí yín, màá mú kí ẹ bímọ lémọ, kí ẹ sì di púpọ̀,+ màá sì mú májẹ̀mú tí mo bá yín dá ṣẹ.+ 10 Bí ẹ ṣe ń jẹ irè oko tó ṣẹ́ kù láti ọdún tó kọjá, ẹ máa ní láti palẹ̀ èyí tó ṣẹ́ kù mọ́ kí tuntun lè wọlé. 11 Màá gbé àgọ́ ìjọsìn mi sáàárín yín,+ mi* ò sì ní kọ̀ yín. 12 Èmi yóò máa rìn láàárín yín, èmi yóò sì jẹ́ Ọlọ́run yín,+ ẹ̀yin ní tiyín, yóò sì jẹ́ èèyàn mi.+ 13 Èmi ni Jèhófà Ọlọ́run yín, tó mú yín kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì, kí ẹ má bàa ṣe ẹrú wọn mọ́. Mo ṣẹ́ àwọn ọ̀pá àjàgà yín, mo sì mú kí ẹ lè nàró ṣánṣán bí ẹ ṣe ń rìn.*

14 “‘Àmọ́, tí ẹ ò bá fetí sí mi, tí ẹ ò sì pa gbogbo àṣẹ yìí mọ́,+ 15 tí ẹ bá kọ àwọn òfin mi,+ tí ẹ* sì kórìíra àwọn ìdájọ́ mi débi pé ẹ ò pa gbogbo àṣẹ mi mọ́, tí ẹ sì da májẹ̀mú mi,+ 16 èmi, ní tèmi, yóò ṣe nǹkan wọ̀nyí sí yín: màá kó ìdààmú bá yín láti fìyà jẹ yín, màá fi ikọ́ ẹ̀gbẹ àti akọ ibà ṣe yín, yóò mú kí ojú yín di bàìbàì, kí ẹ* sì ṣègbé. Lásán ni ẹ máa fún irúgbìn yín, torí àwọn ọ̀tá yín ni yóò jẹ ẹ́.+ 17 Mi ò ní fojúure wò yín, àwọn ọ̀tá yín á sì ṣẹ́gun yín;+ àwọn tó kórìíra yín yóò tẹ̀ yín mọ́lẹ̀,+ ẹ ó sì sá nígbà tí ẹnì kankan ò lé yín.+

18 “‘Tí ẹ ò bá wá fetí sí mi lẹ́yìn èyí, ṣe ni màá fi ìyà ẹ̀ṣẹ̀ yín jẹ yín ní ìlọ́po méje. 19 Màá fòpin sí ìgbéraga yín, màá mú kí ojú ọ̀run yín dà bí irin+ àti ilẹ̀ yín bíi bàbà. 20 Lásán ni ẹ máa lo gbogbo agbára yín, torí ilẹ̀ yín kò ní mú èso rẹ̀ jáde,+ àwọn igi ilẹ̀ yín kò sì ní so èso.

21 “‘Tí ẹ bá ṣì ń kẹ̀yìn sí mi, tí ẹ ò sì fetí sí mi, ṣe ni màá fi ìyà ẹ̀ṣẹ̀ yín jẹ yín ní ìlọ́po méje. 22 Èmi yóò rán àwọn ẹran inú igbó sáàárín yín,+ wọ́n á pa yín lọ́mọ jẹ,+ wọ́n á pa àwọn ẹran ọ̀sìn yín run, wọ́n á dín iye yín kù, àwọn ọ̀nà yín yóò sì dá páropáro.+

23 “‘Lẹ́yìn nǹkan wọ̀nyí, tí ẹ kò bá gba ìbáwí tí mo fún yín,+ tí ẹ ṣì ń kẹ̀yìn sí mi, 24 èmi náà yóò kẹ̀yìn sí yín, èmi fúnra mi yóò sì fìyà jẹ yín ní ìlọ́po méje torí ẹ̀ṣẹ̀ yín. 25 Èmi yóò mú idà ẹ̀san wá sórí yín torí ẹ da májẹ̀mú+ náà. Tí ẹ bá kóra jọ sínú àwọn ìlú yín, èmi yóò rán àrùn sí àárín yín,+ màá sì mú kí ọwọ́ àwọn ọ̀tá yín tẹ̀ yín.+ 26 Tí mo bá run ibi* tí ẹ kó búrẹ́dì*+ yín jọ sí, obìnrin mẹ́wàá ni yóò yan búrẹ́dì yín nínú ààrò kan ṣoṣo, wọ́n á máa wọn búrẹ́dì fún yín;+ ẹ ó jẹ, àmọ́ ẹ ò ní yó.+

27 “‘Lẹ́yìn nǹkan wọ̀nyí, tí ẹ ò bá fetí sí mi, tí ẹ ṣì ń kẹ̀yìn sí mi, 28 èmi yóò túbọ̀ kẹ̀yìn sí yín,+ èmi fúnra mi yóò sì fi ìyà ẹ̀ṣẹ̀ yín jẹ yín ní ìlọ́po méje. 29 Torí náà, ṣe ni ẹ máa jẹ ẹran ara àwọn ọmọkùnrin yín, ẹ ó sì jẹ ẹran ara àwọn ọmọbìnrin yín.+ 30 Èmi yóò run àwọn ibi gíga+ tí ẹ ti ń sin àwọn òrìṣà yín, màá wó àwọn pẹpẹ tùràrí yín lulẹ̀, màá sì to òkú yín jọ pelemọ sórí òkú àwọn òrìṣà ẹ̀gbin*+ yín, èmi* yóò pa yín tì, màá sì kórìíra yín.+ 31 Èmi yóò mú kí idà pa àwọn ìlú yín,+ màá sì sọ àwọn ibi mímọ́ yín di ahoro, mi ò ní gbọ́ òórùn dídùn* àwọn ẹbọ yín. 32 Èmi fúnra mi yóò mú kí ilẹ̀ náà di ahoro,+ àwọn ọ̀tá yín tó ń gbé ibẹ̀ yóò sì máa wò ó tìyanutìyanu.+ 33 Èmi yóò tú yín ká sáàárín àwọn orílẹ̀-èdè,+ màá sì fa idà yọ látinú àkọ̀ láti lé yín bá;+ ilẹ̀ yín yóò di ahoro,+ àwọn ìlú yín yóò sì pa run.

34 “‘Nígbà yẹn, ilẹ̀ náà yóò san àwọn sábáàtì rẹ̀ ní gbogbo ọjọ́ tó bá fi wà ní ahoro, nígbà tí ẹ bá wà ní ilẹ̀ àwọn ọ̀tá yín. Nígbà yẹn, ilẹ̀ náà máa sinmi,* torí ó gbọ́dọ̀ san àwọn sábáàtì rẹ̀ pa dà.+ 35 Yóò sinmi ní gbogbo ọjọ́ tó bá fi wà ní ahoro, torí kò sinmi nígbà àwọn sábáàtì yín, nígbà tí ẹ̀ ń gbé ibẹ̀.

36 “‘Ní ti àwọn tó bá yè é,+ màá fi ìbẹ̀rù kún ọkàn wọn ní ilẹ̀ àwọn ọ̀tá wọn; ìró ewé tí atẹ́gùn ń fẹ́ máa lé wọn sá, wọ́n á fẹsẹ̀ fẹ bí ẹni ń sá fún idà, wọ́n á sì ṣubú láìsí ẹni tó ń lé wọn.+ 37 Wọ́n á kọ lu ara wọn bí ẹni ń sá fún idà, bó tiẹ̀ jẹ́ pé kò sẹ́ni tó ń lé wọn. Ẹ ò ní lè kojú àwọn ọ̀tá yín.+ 38 Ẹ ó ṣègbé láàárín àwọn orílẹ̀-èdè,+ ilẹ̀ àwọn ọ̀tá yín yóò sì jẹ yín run. 39 Àwọn tó bá ṣẹ́ kù nínú yín máa jẹrà sí ilẹ̀ àwọn ọ̀tá yín+ torí ẹ̀ṣẹ̀ yín. Àní, wọn yóò jẹrà dà nù torí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn bàbá wọn.+ 40 Wọ́n á wá jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ ara wọn+ àti ẹ̀ṣẹ̀ àwọn bàbá wọn pẹ̀lú ìwà àìṣòótọ́ àwọn bàbá wọn, wọ́n á sì gbà pé àwọn ti hùwà àìṣòótọ́ torí wọ́n kẹ̀yìn sí mi.+ 41 Èmi náà sì kẹ̀yìn sí wọn,+ torí mo mú wọn wá sí ilẹ̀ àwọn ọ̀tá wọn.+

“‘Bóyá nígbà yẹn, wọ́n á rẹ ọkàn wọn tí wọn ò kọ nílà* wálẹ̀,+ wọ́n á sì wá jìyà ẹ̀ṣẹ̀ wọn. 42 Màá sì rántí májẹ̀mú tí mo bá Jékọ́bù dá+ àti májẹ̀mú tí mo bá Ísákì dá,+ màá rántí májẹ̀mú tí mo bá Ábúráhámù dá,+ màá sì rántí ilẹ̀ náà. 43 Nígbà tí wọ́n pa ilẹ̀ náà tì, ó ń san àwọn sábáàtì rẹ̀,+ ó wà ní ahoro nígbà tí wọn ò sí níbẹ̀, wọ́n sì ń jìyà ẹ̀ṣẹ̀ wọn, torí wọ́n kọ àwọn ìdájọ́ mi, wọ́n* sì kórìíra àwọn àṣẹ mi.+ 44 Àmọ́ láìka gbogbo èyí sí, nígbà tí wọ́n ṣì wà ní ilẹ̀ àwọn ọ̀tá wọn, mi ò ní kọ̀ wọ́n pátápátá+ tàbí kí n ta wọ́n nù débi pé màá pa wọ́n run pátápátá, torí ìyẹn á da májẹ̀mú tí mo bá wọn dá,+ torí èmi ni Jèhófà Ọlọ́run wọn. 45 Nítorí wọn, màá rántí májẹ̀mú tí mo bá àwọn baba ńlá wọn dá,+ àwọn tí mo mú kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì níṣojú àwọn orílẹ̀-èdè,+ láti fi hàn pé èmi ni Ọlọ́run wọn. Èmi ni Jèhófà.’”

46 Èyí ni àwọn ìlànà, àwọn ìdájọ́ àti àwọn òfin tí Jèhófà gbé kalẹ̀ láàárín òun àti àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lórí Òkè Sínáì nípasẹ̀ Mósè.+

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́