SÍ ÀWỌN ARÁ FÍLÍPÌ
1 Pọ́ọ̀lù àti Tímótì, àwa ẹrú Kristi Jésù, sí gbogbo ẹni mímọ́ nínú Kristi Jésù, tí wọ́n wà ní ìlú Fílípì,+ pẹ̀lú àwọn alábòójútó àti àwọn ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́:+
2 Kí ẹ ní inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí àti àlàáfíà látọ̀dọ̀ Baba wa Ọlọ́run àti Jésù Kristi Olúwa.
3 Mò ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run mi ní gbogbo ìgbà tí mo bá rántí yín 4 nínú gbogbo ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀ mi lórí gbogbo yín. Inú mi máa ń dùn ní gbogbo ìgbà tí mo bá ń rawọ́ ẹ̀bẹ̀,+ 5 nítorí ìtìlẹyìn tí ẹ ti ṣe fún* ìhìn rere láti ọjọ́ àkọ́kọ́ títí di àkókò yìí. 6 Nítorí ohun kan dá mi lójú, pé ẹni tó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ rere nínú yín á ṣe é parí+ tó bá fi máa di ọjọ́ Kristi Jésù.+ 7 Ó tọ́ tí mo bá ronú lọ́nà yìí nípa gbogbo yín, torí ọ̀rọ̀ yín ń jẹ mí lọ́kàn, ẹ sì jẹ́ alájọpín pẹ̀lú mi nínú inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí nínú àwọn ìdè ẹ̀wọ̀n mi+ àti nínú bí a ṣe ń gbèjà ìhìn rere, tí a sì ń fìdí rẹ̀ múlẹ̀ lọ́nà òfin.+
8 Mo fi Ọlọ́run ṣe ẹlẹ́rìí pé àárò gbogbo yín ń sọ mí nítorí ìfẹ́ oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́, irú èyí tí Kristi Jésù ní. 9 Ohun tí mò ń gbà ládùúrà ni pé kí ìfẹ́ yín lè túbọ̀ pọ̀ gidigidi,+ kí ẹ sì ní ìmọ̀ tó péye+ àti òye tó kún rẹ́rẹ́;+ 10 pé kí ẹ lè máa wádìí dájú àwọn ohun tó ṣe pàtàkì jù,+ kí ẹ lè jẹ́ aláìní àbààwọ́n, kí ẹ má sì máa mú àwọn ẹlòmíì kọsẹ̀+ títí di ọjọ́ Kristi; 11 kí èso òdodo tó wá nípasẹ̀ Jésù Kristi lè kún inú yín,+ fún ògo àti ìyìn Ọlọ́run.
12 Ní báyìí, ẹ̀yin ará, mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ pé àwọn ohun tó ṣẹlẹ̀ sí mi ti mú kí ìhìn rere tẹ̀ síwájú, 13 tó fi jẹ́ pé gbogbo èèyàn mọ̀+ nípa àwọn ìdè ẹ̀wọ̀n mi+ nítorí Kristi láàárín gbogbo Ẹ̀ṣọ́ Ọba àti gbogbo àwọn yòókù. 14 Púpọ̀ lára àwọn ará nínú Olúwa ti ní ìgboyà nítorí àwọn ìdè ẹ̀wọ̀n mi, wọ́n sì túbọ̀ ń fi ìgboyà sọ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run láìbẹ̀rù.
15 Lóòótọ́, àwọn kan ń wàásù Kristi nítorí owú àti ìdíje, àmọ́ àwọn míì ń ṣe bẹ́ẹ̀ nítorí inú rere. 16 Ìfẹ́ ló ń mú kí àwọn ti ìkẹyìn yìí máa kéde Kristi, torí wọ́n mọ̀ pé a ti yàn mí láti gbèjà ìhìn rere;+ 17 àmọ́ torí àtidá ìjà sílẹ̀ ni àwọn ti ìṣáájú fi ń ṣe bẹ́ẹ̀, kì í ṣe torí pé wọ́n ní èrò tó dáa, ṣe ni wọ́n fẹ́ dá wàhálà sílẹ̀ fún mi nínú àwọn ìdè ẹ̀wọ̀n mi. 18 Kí ló ti wá yọrí sí? Ní gbogbo ọ̀nà, ì báà jẹ́ nínú dídíbọ́n tàbí ní òótọ́, à ń kéde Kristi, èyí sì ń múnú mi dùn. Kódà, ṣe ni inú mi á túbọ̀ máa dùn, 19 torí mo mọ̀ pé èyí máa yọrí sí ìgbàlà mi nípasẹ̀ ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀ yín+ àti ìtìlẹyìn ẹ̀mí Jésù Kristi.+ 20 Èyí bá ohun tí mò ń fojú sọ́nà fún, tí mo sì ń retí mu, pé ojú ò ní tì mí lọ́nàkọnà, àmọ́ pé nínú bí mo ṣe lómìnira láti sọ̀rọ̀ fàlàlà, a ó ti ara mi gbé Kristi ga báyìí, bí a ṣe ń gbé e ga tẹ́lẹ̀, ì báà jẹ́ nípasẹ̀ ìyè tàbí nípasẹ̀ ikú.+
21 Ní tèmi, tí mo bá wà láàyè, mo wà láàyè fún Kristi,+ tí mo bá sì kú, èrè ló jẹ́ fún mi.+ 22 Ní báyìí, tí mo bá máa wà láàyè nìṣó nínú ara, ó jẹ́ èrè iṣẹ́ mi; síbẹ̀, mi ò sọ ohun tí màá yàn fún ẹnikẹ́ni. 23 Mi ò mọ èyí tí màá mú nínú nǹkan méjì tó wà níwájú mi yìí, torí ó wù mí kí n gba ìtúsílẹ̀, kí n sì wà pẹ̀lú Kristi,+ torí ó dájú pé, ìyẹn ló sàn jù.+ 24 Àmọ́ ṣá o, kí n ṣì wà nínú ẹran ara ló máa ṣe yín láǹfààní jù lọ. 25 Nítorí náà, bí èyí ṣe dá mi lójú, mo mọ̀ pé màá dúró, màá sì wà pẹ̀lú gbogbo yín kí ẹ lè tẹ̀ síwájú, kí inú yín sì máa dùn nínú ìgbàgbọ́, 26 kí ayọ̀ yín lè kún nínú Kristi Jésù nítorí mi nígbà tí mo bá tún wà pẹ̀lú yín.
27 Kìkì pé kí ẹ máa hùwà* lọ́nà tó yẹ ìhìn rere nípa Kristi,+ kó lè jẹ́ pé, bóyá mo wá wò yín tàbí mi ò wá, kí n lè máa gbọ́ nípa yín pé ẹ dúró gbọn-in nínú ẹ̀mí kan, pẹ̀lú ọkàn kan,*+ ẹ jọ ń sapá nítorí ìgbàgbọ́ nínú ìhìn rere, 28 ẹ ò sì jẹ́ kí àwọn tó ń ta kò yín kó jìnnìjìnnì bá yín lọ́nàkọnà. Èyí jẹ́ àmì ìparun+ fún wọn, àmọ́ ó jẹ́ ti ìgbàlà fún yín;+ ọ̀dọ̀ Ọlọ́run ló sì ti wá. 29 A ti fún yín ní àǹfààní náà nítorí Kristi, kì í ṣe láti ní ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀ nìkan, àmọ́ láti jìyà nítorí rẹ̀ pẹ̀lú.+ 30 Irú ìjàkadì tí ẹ rí i pé mò ń jà ni ẹ̀yin náà ń jà,+ òun náà lẹ gbọ́ pé mo ṣì wà lẹ́nu rẹ̀.
2 Nígbà náà, tí ìṣírí èyíkéyìí bá wà nínú Kristi, tí ìtùnú onífẹ̀ẹ́ èyíkéyìí bá wà, tí àjọṣe tẹ̀mí* èyíkéyìí bá wà, tí ìfẹ́ oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ àti àánú bá wà, 2 ẹ jẹ́ kí èrò yín àti ìfẹ́ yín ṣọ̀kan kí ẹ lè mú ayọ̀ mi kún, kí ẹ wà níṣọ̀kan délẹ̀délẹ̀,* kí ẹ sì ní èrò kan náà lọ́kàn.+ 3 Ẹ má ṣe jẹ́ kí ìbínú+ tàbí ìgbéraga+ mú yín ṣe ohunkóhun, àmọ́ ẹ jẹ́ kí ìrẹ̀lẹ̀* máa mú kí ẹ gbà pé àwọn míì sàn jù yín lọ,+ 4 bí ẹ ṣe ń wá ire àwọn ẹlòmíì,+ kì í ṣe tiyín nìkan.+
5 Ẹ ní èrò yìí nínú yín, irú èyí tí Kristi Jésù náà ní,+ 6 ẹni tó jẹ́ pé, bí ó tiẹ̀ wà ní ìrísí Ọlọ́run,+ kò rò ó rárá pé òun fẹ́ bá Ọlọ́run dọ́gba.+ 7 Ó tì o, àmọ́ ó fi gbogbo ohun tó ní sílẹ̀, ó gbé ìrísí ẹrú wọ̀,+ ó sì di èèyàn.*+ 8 Jù bẹ́ẹ̀ lọ, nígbà tó wá ní ìrí èèyàn,* ó rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀, ó sì di onígbọràn títí dé ojú ikú,+ bẹ́ẹ̀ ni, ikú lórí òpó igi oró.*+ 9 Torí ìdí yìí gan-an ni Ọlọ́run ṣe gbé e sí ipò gíga,+ tó sì fún un ní orúkọ tó lékè gbogbo orúkọ mìíràn,+ 10 kó lè jẹ́ pé ní orúkọ Jésù, kí gbogbo eékún máa wólẹ̀, ti àwọn tó wà lọ́run àti àwọn tó wà láyé pẹ̀lú àwọn tó wà lábẹ́ ilẹ̀,+ 11 kí gbogbo ahọ́n sì máa jẹ́wọ́ ní gbangba pé Jésù Kristi ni Olúwa+ fún ògo Ọlọ́run tó jẹ́ Baba.
12 Nítorí náà, ẹ̀yin ará mi ọ̀wọ́n, bí ẹ ṣe ń ṣègbọràn ní gbogbo ìgbà, tí kì í ṣe nígbà tí mo bá wà lọ́dọ̀ yín nìkan, àmọ́ ní báyìí, ẹ túbọ̀ ń ṣe bẹ́ẹ̀ nígbà tí mi ò sí lọ́dọ̀ yín, ẹ máa ṣiṣẹ́ ìgbàlà yín yọrí pẹ̀lú ìbẹ̀rù àti ìwárìrì. 13 Torí Ọlọ́run ni ẹni tó ń fún yín lágbára nítorí ìdùnnú rẹ̀, ó ń mú kó wù yín láti gbé ìgbésẹ̀, ó sì ń fún yín ní agbára láti ṣe é. 14 Ẹ máa ṣe ohun gbogbo láìsí ìkùnsínú+ àti ìjiyàn,+ 15 kí ẹ lè jẹ́ aláìlẹ́bi àti ọlọ́wọ́ mímọ́, ọmọ Ọlọ́run+ tí kò ní àbààwọ́n láàárín ìran onímàgòmágó àti oníwà ìbàjẹ́,+ láàárín àwọn tí ẹ ti ń tàn bí ìmọ́lẹ̀ nínú ayé,+ 16 bí ẹ ṣe ń di ọ̀rọ̀ ìyè mú ṣinṣin.+ Nígbà náà, màá lè ní ìdí láti yọ̀ ní ọjọ́ Kristi, bí mo ṣe mọ̀ pé mi ò sáré lásán, mi ò sì ṣiṣẹ́ kára lásán. 17 Àmọ́, bí a tilẹ̀ ń tú mi jáde bí ọrẹ ohun mímu+ sórí ẹbọ+ àti iṣẹ́ mímọ́* tí ìgbàgbọ́ yín ń mú kí ẹ ṣe, inú mi ń dùn, mo sì bá gbogbo yín yọ̀. 18 Bákan náà, ó yẹ kí inú tiyín náà máa dùn, kí ẹ sì máa bá mi yọ̀.
19 Ní báyìí, mo ní ìrètí pé, tí Jésù Olúwa bá fẹ́, màá rán Tímótì+ sí yín láìpẹ́, kí ara mi lè yá gágá nígbà tí mo bá gbọ́ ìròyìn nípa yín. 20 Nítorí mi ò ní ẹlòmíì tó níwà bíi tirẹ̀ tó máa fi òótọ́ inú bójú tó ọ̀rọ̀ yín. 21 Torí gbogbo àwọn yòókù ń wá ire ara wọn, kì í ṣe ti Jésù Kristi. 22 Àmọ́, ẹ mọ ẹ̀rí tó fi hàn nípa ara rẹ̀, pé bí ọmọ+ lọ́dọ̀ bàbá ni ó ṣẹrú pẹ̀lú mi kí ìhìn rere lè máa tẹ̀ síwájú. 23 Nítorí náà, òun ni mo retí pé màá rán ní gbàrà tí mo bá ti mọ ibi tí ọ̀rọ̀ mi máa já sí. 24 Lóòótọ́, ó dá mi lójú nínú Olúwa pé èmi fúnra mi máa wá láìpẹ́.+
25 Àmọ́ ní báyìí, mo rí i pé á dáa kí n rán Ẹpafíródítù sí yín, arákùnrin mi tí a jọ ń ṣiṣẹ́ àti ọmọ ogun ẹlẹgbẹ́ mi, ó tún jẹ́ aṣojú yín àti ìránṣẹ́ tó ń bá mi ṣe ohun tí mo bá fẹ́ ṣe,+ 26 nítorí ó ń wù ú láti rí gbogbo yín, ó sì ní ẹ̀dùn ọkàn torí ẹ ti gbọ́ pé ó ṣàìsàn. 27 Òótọ́ ni pé ó ṣàìsàn débi pé ó fẹ́rẹ̀ẹ́ kú; àmọ́ Ọlọ́run ṣàánú rẹ̀, kódà, kì í ṣe òun nìkan, ó ṣàánú èmi náà, kí n má bàa ní ìbànújẹ́ kún ìbànújẹ́. 28 Nítorí náà, mò ń rán an ní kíá láìjáfara, kí inú yín lè dùn lẹ́ẹ̀kan sí i nígbà tí ẹ bá rí i, kí àníyàn tèmi náà sì lè dín kù. 29 Torí náà, ẹ fi ayọ̀ gbà á tọwọ́tẹsẹ̀ bí ẹ ṣe máa ń gba àwọn ọmọlẹ́yìn Olúwa, ẹ sì máa ka irú àwọn èèyàn bẹ́ẹ̀ sí ẹni ọ̀wọ́n,+ 30 torí pé ó fẹ́rẹ̀ẹ́ kú nítorí iṣẹ́ Kristi,* ó fi ẹ̀mí* rẹ̀ wewu kó lè ṣe àwọn ohun tí ẹ̀yin ì bá ṣe fún mi ká ní ẹ wà níbí.+
3 Lákòótán, ẹ̀yin ará mi, ẹ máa yọ̀ nínú Olúwa.+ Kò ni mí lára láti kọ̀wé nípa àwọn ohun kan náà sí yín, torí ààbò yín sì ni.
2 Ẹ máa ṣọ́ra fún àwọn ajá; ẹ máa ṣọ́ra fún àwọn oníṣẹ́ ibi; ẹ máa ṣọ́ra fún àwọn tó ń kọ ara nílà.+ 3 Nítorí àwa ni a dádọ̀dọ́* lóòótọ́,+ àwa tí à ń ṣe iṣẹ́ ìsìn mímọ́ nípasẹ̀ ẹ̀mí Ọlọ́run, tí à ń fi Kristi Jésù yangàn,+ tí a ò sì gbẹ́kẹ̀ lé ẹran ara, 4 torí náà, tí a bá rí ẹnikẹ́ni tó ní ìdí láti gbẹ́kẹ̀ lé ẹran ara, èmi gan-an ní.
Tí ẹlòmíì bá sì rò pé òun ní ìdí láti gbẹ́kẹ̀ lé ẹran ara, tèmi jù bẹ́ẹ̀: 5 mo dádọ̀dọ́* ní ọjọ́ kẹjọ,+ mo jẹ́ ọmọ orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì, mo wá láti ẹ̀yà Bẹ́ńjámínì, Hébérù tó jẹ́ ọmọ bíbí àwọn Hébérù;+ ní ti òfin, mo jẹ́ Farisí;+ 6 ní ti ìtara, mo ṣe inúnibíni sí ìjọ;+ ní ti jíjẹ́ olódodo nínú pípa òfin mọ́, mo jẹ́ aláìlẹ́bi. 7 Síbẹ̀, àwọn ohun tó jẹ́ èrè fún mi ni mo ti kà sí àdánù* nítorí Kristi.+ 8 Yàtọ̀ síyẹn, mo ti ka ohun gbogbo sí àdánù nítorí ìmọ̀ nípa Kristi Jésù Olúwa mi ṣeyebíye ju ohun gbogbo lọ. Nítorí rẹ̀, mo ti gbé ohun gbogbo sọ nù, mo sì kà wọ́n sí ọ̀pọ̀ pàǹtírí,* kí n lè jèrè Kristi, 9 kí ó sì hàn pé mo wà ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú rẹ̀, kì í ṣe nítorí òdodo tèmi nínú pípa Òfin mọ́, àmọ́ ó jẹ́ nítorí òdodo tó wá nípasẹ̀ ìgbàgbọ́ + nínú Kristi,+ òdodo tó wá látọ̀dọ̀ Ọlọ́run, tó sì dá lórí ìgbàgbọ́.+ 10 Mo fẹ́ mọ Kristi àti agbára àjíǹde rẹ̀,+ kí n jẹ irú ìyà tó jẹ,+ kí n sì kú irú ikú tó kú,+ 11 kí n lè rí i bóyá lọ́nàkọnà, ọwọ́ mi á tẹ àjíǹde àkọ́kọ́ kúrò nínú ikú.+
12 Kì í ṣe pé mo ti rí i gbà tàbí pé a ti sọ mí di pípé, àmọ́ mò ń sapá+ bóyá ọwọ́ mi á lè tẹ ohun tí Kristi Jésù torí rẹ̀ yàn mí.*+ 13 Ẹ̀yin ará, mi ò ka ara mi sí ẹni tí ọwọ́ rẹ̀ ti tẹ̀ ẹ́; àmọ́ ohun kan tó dájú ni pé: Bí mo ṣe ń gbàgbé àwọn ohun tí mo fi sílẹ̀ sẹ́yìn,+ tí mo sì ń nàgà sí àwọn ohun tó wà níwájú,+ 14 mò ń sapá kí ọwọ́ mi lè tẹ èrè+ ìpè+ Ọlọ́run sí òkè nípasẹ̀ Kristi Jésù. 15 Nítorí náà, ẹ jẹ́ kí àwa tí a ti dàgbà+ ní èrò yìí, tí èrò yín bá sì yàtọ̀ lọ́nà èyíkéyìí, Ọlọ́run á jẹ́ kí ẹ ní èrò tí mo sọ yìí. 16 Àmọ́ ṣá, níbi tí a tẹ̀ síwájú dé, ẹ jẹ́ kí a máa rìn létòlétò ní ọ̀nà kan náà.
17 Ẹ̀yin ará, kí gbogbo yín máa fara wé mi,+ kí ẹ sì tẹ ojú yín mọ́ àwọn tó ń rìn lọ́nà tó bá àpẹẹrẹ tí a fi lélẹ̀ fún yín mu. 18 Nítorí ọ̀pọ̀ èèyàn ló wà, mo sábà máa ń mẹ́nu kàn wọ́n tẹ́lẹ̀, ní báyìí tẹkúntẹkún ni mò ń mẹ́nu kàn wọ́n, àwọn tí wọ́n ń hùwà bí ọ̀tá òpó igi oró* Kristi. 19 Ìparun ni ìgbẹ̀yìn wọn, ikùn wọn ni ọlọ́run wọn, ohun ìtìjú ni wọ́n fi ń ṣògo, àwọn nǹkan ti ayé ni wọ́n sì ń rò.+ 20 Àmọ́, ìlú ìbílẹ̀ wa*+ wà ní ọ̀run,+ a sì ń dúró de olùgbàlà láti ibẹ̀ lójú méjèèjì, ìyẹn Jésù Kristi Olúwa,+ 21 ẹni tó máa fi agbára ńlá rẹ̀ yí ara rírẹlẹ̀ wa pa dà kí ó lè dà bí* ara ológo tirẹ̀,+ èyí tó mú kó lè fi ohun gbogbo sábẹ́ ara rẹ̀.+
4 Nítorí náà, ẹ̀yin ará mi tí mo nífẹ̀ẹ́, tó sì ń wù mí láti rí, ẹ̀yin tí ẹ jẹ́ ìdùnnú mi àti adé mi,+ ẹ dúró gbọn-in+ ní ọ̀nà yìí nínú Olúwa, ẹ̀yin ará mi ọ̀wọ́n.
2 Mo rọ Yúódíà, mo sì rọ Síńtíkè pé kí wọ́n ní èrò kan náà nínú Olúwa.+ 3 Bẹ́ẹ̀ ni, mo fẹ́ kí ìwọ náà, gẹ́gẹ́ bí alábàáṣiṣẹ́ tòótọ́,* máa ṣèrànwọ́ fún àwọn obìnrin yìí, wọ́n ti sapá* pẹ̀lú mi nítorí ìhìn rere, pẹ̀lú Kílẹ́mẹ́ǹtì àti àwọn yòókù tí a jọ ń ṣiṣẹ́, àwọn tí orúkọ wọn wà nínú ìwé ìyè.+
4 Ẹ máa yọ̀ nígbà gbogbo nínú Olúwa. Lẹ́ẹ̀kan sí i, mo sọ pé, Ẹ máa yọ̀!+ 5 Ẹ jẹ́ kí gbogbo èèyàn rí i pé ẹ̀ ń fòye báni lò.+ Olúwa wà nítòsí. 6 Ẹ má ṣe máa ṣàníyàn nípa ohunkóhun,+ àmọ́ nínú ohun gbogbo nípasẹ̀ àdúrà àti ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀ pẹ̀lú ìdúpẹ́, ẹ máa sọ àwọn ohun tí ẹ̀ ń tọrọ fún Ọlọ́run;+ 7 àlàáfíà Ọlọ́run+ tó kọjá gbogbo òye yóò sì máa ṣọ́ ọkàn yín+ àti agbára ìrònú yín* nípasẹ̀ Kristi Jésù.
8 Paríparí rẹ̀, ẹ̀yin ará, ohunkóhun tó jẹ́ òótọ́, ohunkóhun tó ṣe pàtàkì, ohunkóhun tó jẹ́ òdodo, ohunkóhun tó jẹ́ mímọ́,* ohunkóhun tó yẹ ní fífẹ́, ohunkóhun tí à ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ dáadáa, ohunkóhun tó bá dára, ohunkóhun tó bá yẹ fún ìyìn, ẹ máa ronú* lórí àwọn nǹkan yìí.+ 9 Àwọn ohun tí ẹ kọ́, tí ẹ tẹ́wọ́ gbà, tí ẹ gbọ́, tí ẹ sì rí lọ́dọ̀ mi, ẹ máa fi wọ́n sílò,+ Ọlọ́run àlàáfíà yóò sì wà pẹ̀lú yín.
10 Mo yọ̀ gidigidi nínú Olúwa pé ní báyìí ẹ ti jẹ́ kí ọ̀rọ̀ mi pa dà máa jẹ yín lọ́kàn.+ Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ọ̀rọ̀ mi ń jẹ yín lọ́kàn tẹ́lẹ̀, ẹ ò rí àyè láti fi hàn bẹ́ẹ̀. 11 Kì í ṣe torí pé mi ò ní ohun tí mo nílò ni mo ṣe ń sọ̀rọ̀ yìí, torí mo ti kọ́ bí èèyàn ṣe ń nítẹ̀ẹ́lọ́rùn pẹ̀lú ohun tó bá ní* nínú ipòkípò tí mo bá wà.+ 12 Mo mọ bí èèyàn ṣe ń gbé nínú àìní,*+ mo sì mọ bí èèyàn ṣe ń gbé nínú ọ̀pọ̀. Nínú ohun gbogbo àti ní ipòkípò, mo ti kọ́ àṣírí bí a ṣe ń jẹ àjẹyó àti bí a ṣe ń wà nínú ebi, bí a ṣe ń ní púpọ̀ àti bí a ṣe ń jẹ́ aláìní. 13 Mo ní okun láti ṣe ohun gbogbo nípasẹ̀ ẹni tó ń fún mi lágbára.+
14 Síbẹ̀, ẹ ṣe dáadáa bí ẹ ṣe ràn mí lọ́wọ́ nínú ìpọ́njú mi. 15 Kódà, ẹ̀yin ará Fílípì náà mọ̀ pé lẹ́yìn tí ẹ kọ́kọ́ gbọ́ ìhìn rere, nígbà tí mo kúrò ní Makedóníà, kò sí ìjọ kan tó bá mi dá sí ọ̀rọ̀ fífúnni àti gbígbà, àfi ẹ̀yin nìkan;+ 16 torí nígbà tí mo wà ní Tẹsalóníkà, ẹ fi nǹkan tí mo nílò ránṣẹ́ sí mi, kì í ṣe ẹ̀ẹ̀kan péré, ẹ̀ẹ̀mejì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni. 17 Kì í ṣe pé mò ń wá ẹ̀bùn, ohun rere tó máa mú èrè púpọ̀ sí i wá fún yín ni mò ń wá. 18 Àmọ́, mo ní ohun gbogbo tí mo nílò, kódà mo ní jù bẹ́ẹ̀ lọ. Mo ti ní ànító, ní báyìí tí àwọn ohun tí ẹ fi rán Ẹpafíródítù+ ti dé ọwọ́ mi, wọ́n dà bí òórùn dídùn,+ ẹbọ tó ṣe ìtẹ́wọ́gbà, tó sì wu Ọlọ́run gidigidi. 19 Nítorí náà, Ọlọ́run mi tí ọrọ̀ rẹ̀ kò lópin máa pèsè gbogbo ohun tí ẹ nílò pátápátá+ nípasẹ̀ Kristi Jésù. 20 Ọlọ́run wa àti Baba ni kí ògo jẹ́ tirẹ̀ títí láé àti láéláé. Àmín.
21 Ẹ bá mi kí gbogbo àwọn ẹni mímọ́ nínú Kristi Jésù. Àwọn ará tó wà pẹ̀lú mi kí yín. 22 Gbogbo ẹni mímọ́, ní pàtàkì àwọn tó jẹ́ ti agbo ilé Késárì,+ kí yín.
23 Kí inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Jésù Kristi Olúwa wà pẹ̀lú ẹ̀mí tí ẹ fi hàn.
Tàbí “nítorí bí ẹ ṣe lọ́wọ́ sí ìtẹ̀síwájú.”
Tàbí “kí ẹ máa ṣe ohun tó fi hàn pé ẹ jẹ́ ọmọ ìbílẹ̀.”
Tàbí “ní ìṣọ̀kan.”
Ní Grk., “àjọpín nínú ẹ̀mí.”
Tàbí “kí ọkàn yín ṣọ̀kan.”
Tàbí “ìrẹ̀lẹ̀ ọkàn.”
Ní Grk., “ó sì wá wà ní ìrí èèyàn.”
Ní Grk., “nígbà tó rí ara rẹ̀ ní ìrísí èèyàn.”
Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.
Tàbí “iṣẹ́ fún àwọn èèyàn.”
Tàbí kó jẹ́, “iṣẹ́ Olúwa.”
Tàbí “ọkàn.”
Tàbí “kọlà.”
Tàbí “kọlà.”
Tàbí kó jẹ́, “fi sílẹ̀ tinútinú.”
Tàbí “ìdọ̀tí.”
Ní Grk., “gbé ọwọ́ lé mi.”
Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.
Ní Grk., “ẹ̀tọ́ wa láti jẹ́ aráàlú.”
Ní Grk., “bára mu pẹ̀lú.”
Ní Grk., “alájọru àjàgà tòótọ́.”
Tàbí “ṣiṣẹ́ kára.”
Tàbí “èrò yín.”
Tàbí “tó mọ́.”
Tàbí “ṣàṣàrò.”
Tàbí “ní ẹ̀mí ohun-moní-tómi.”
Tàbí “pẹ̀lú ìpèsè bín-ń-tín.”