Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìṣàkóso Ọlọ́run Fún 1999
Àwọn Ìtọ́ni
Ní ọdún 1999, àwọn ohun tí ó tẹ̀ lé e yìí ni yóò jẹ́ ìṣètò fún dídarí Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìṣàkóso Ọlọ́run.
ÀWỌN ÌWÉ ÌKẸ́KỌ̀Ọ́: Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun [bi12-YR], Ilé Ìṣọ́ [w-YR], Jí! [g-YR], Àṣírí Ayọ̀ Ìdílé [fy-YR], àti “Àwọn Àkòrí Ọ̀rọ̀ Bíbélì fún Ìjíròrò” gẹ́gẹ́ bí ó ṣe wà nínú Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun [td-YR] ni àwọn ibi tí a óò gbé iṣẹ́ àyànfúnni kà.
Kí a bẹ̀rẹ̀ ilé ẹ̀kọ́ náà LÁKÒÓKÒ, pẹ̀lú orin, àdúrà, àti àwọn ọ̀rọ̀ ìkíni káàbọ̀, kí a sì tẹ̀ síwájú gẹ́gẹ́ bí ó ṣe tẹ̀ lé e yìí:
IṢẸ́ ÀYÀNFÚNNI NO. 1: Ìṣẹ́jú 15. Alàgbà tàbí ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ ni kí ó bójú tó èyí, a óò sì gbé e ka Ilé Ìṣọ́ tàbí Jí! Kí a ṣe iṣẹ́ àyànfúnni yìí gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ ìtọ́ni oníṣẹ̀ẹ́jú 15, láìsí àtúnyẹ̀wò aláfẹnusọ. Ète rẹ̀ kò gbọ́dọ̀ jẹ́ láti wulẹ̀ kárí ibi tí a yàn fúnni, bí kò ṣe láti pa àfiyèsí pọ̀ sórí ìwúlò gbígbéṣẹ́ tí ó wà nínú ìsọfúnni tí a ń jíròrò, ní títẹnu mọ́ ohun tí yóò ṣe ìjọ láǹfààní jù lọ. Ẹṣin ọ̀rọ̀ tí a yàn ni kí a lò.
Àwọn arákùnrin tí a yan ọ̀rọ̀ àsọyé yìí fún ní láti ṣọ́ra láti má ṣe kọjá àkókò tí a fún wọn. Bí a bá fún wọn ní ìmọ̀ràn ìdákọ́ńkọ́, kí a kọ èyí sínú ìwé ìmọ̀ràn ọ̀rọ̀ sísọ wọn.
ÀWỌN KÓKÓ PÀTÀKÌ LÁTI INÚ BÍBÉLÌ KÍKÀ: Ìṣẹ́jú 6. Èyí ni kí a bójú tó láti ọwọ́ alàgbà tàbí ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ tí yóò mú àkójọpọ̀ ọ̀rọ̀ náà bá àwọn àìní àdúgbò mu lọ́nà tí ó gbéṣẹ́. Èyí kò ní wulẹ̀ jẹ́ àkópọ̀ lórí ibi tí a yàn fún kíkà nìkan. A lè fi ṣíṣe àtúnyẹ̀wò gbogbo orí tí a yàn fúnni láàárín ààbọ̀ ìṣẹ́jú sí ìṣẹ́jú kan kún un. Ṣùgbọ́n, olórí ète náà ni láti ran àwùjọ lọ́wọ́ láti lóye ìdí tí ìsọfúnni náà fi ṣeyebíye fún wa àti bí ó ti ṣeyebíye tó fún wa. Lẹ́yìn náà, alábòójútó ilé ẹ̀kọ́ yóò yọ̀ǹda àwọn ọmọ ilé ẹ̀kọ́ láti lọ sí kíláàsì wọn ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀.
IṢẸ́ ÀYÀNFÚNNI NO. 2: Ìṣẹ́jú 5. Èyí jẹ́ Bíbélì kíkà lórí ibi tí a yàn fúnni tí arákùnrin kan yóò bójú tó. Èyí yóò rí bẹ́ẹ̀ ní ilé ẹ̀kọ́ kìíní àti ní àwọn àwùjọ yòókù tí ó jẹ́ àfikún. Ìwé kíkà tí a yàn fúnni sábà máa ń mọ níwọ̀n tí yóò jẹ́ kí akẹ́kọ̀ọ́ náà lè ṣe àlàyé ṣókí ní ìbẹ̀rẹ̀ àti ní ìparí ọ̀rọ̀ rẹ̀. A lè fi ìtàn tí ó yí àwọn ẹsẹ náà ká, ìjẹ́pàtàkì àsọtẹ́lẹ̀ tàbí ẹ̀kọ́ inú rẹ̀, àti bí àwọn ìlànà rẹ̀ ṣe kàn wá kún un. Kí a ka gbogbo ẹsẹ tí a yàn fúnni pátá, láìdánudúró lágbede méjì láti ṣàlàyé ohunkóhun. Àmọ́ ṣá o, níbi tí àwọn ẹsẹ tí a óò kà kò bá ti tẹ̀ léra, akẹ́kọ̀ọ́ náà lè sọ ẹsẹ tí ó ti ń bá kíkà náà lọ.
IṢẸ́ ÀYÀNFÚNNI NO. 3: Ìṣẹ́jú 5. Arábìnrin ni a óò yan èyí fún. A óò gbé kókó ẹ̀kọ́ iṣẹ́ yìí ka ìwé Àṣírí Ayọ̀ Ìdílé tàbí “Àwọn Àkòrí Ọ̀rọ̀ Bíbélì fún Ìjíròrò” gẹ́gẹ́ bí ó ṣe wà nínú Ìtumọ̀ Ayé Tuntun. A lè gbé e kalẹ̀ lọ́nà ìjẹ́rìí aláìjẹ́-bí-àṣà, ìpadàbẹ̀wò tàbí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé, tàbí apá mìíràn nínú iṣẹ́ ìsìn pápá. Nínú àwọn ọ̀ràn kan, ó lè jẹ́ òbí kan tí ń ṣàjọpín ìsọfúnni pẹ̀lú ọmọ aláìtójúúbọ́ kan. Àwọn tí ń kópa sì lè jókòó tàbí kí wọ́n dúró. Ọ̀nà tí akẹ́kọ̀ọ́ gbà ran onílé tàbí ọmọ náà lọ́wọ́ láti ronú lórí àkójọpọ̀ ọ̀rọ̀, kí ó sì lóye bí ó ṣe lo àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ ni yóò jẹ alábòójútó ilé ẹ̀kọ́ lọ́kàn jù lọ. Akẹ́kọ̀ọ́ tí a yan iṣẹ́ yìí fún gbọ́dọ̀ mọ̀wéékà. Alábòójútó ilé ẹ̀kọ́ yóò ṣètò fún olùrànlọ́wọ́ kan ṣoṣo, ṣùgbọ́n a lè lo olùrànlọ́wọ́ mìíràn ní àfikún. Akẹ́kọ̀ọ́ náà lè pinnu bóyá òun yóò jẹ́ kí onílé ka àwọn ìpínrọ̀ kan nínú ìwé náà, tàbí bẹ́ẹ̀ kọ́ nígbà tí ó bá ń ṣàgbéyẹ̀wò ìwé Ayọ̀ Ìdílé. Ọ̀nà tí ó gbéṣẹ́ tí a gbà lo àkójọpọ̀ ọ̀rọ̀ ni kí a fún ní àfiyèsí pàtàkì, kì í ṣe ọ̀nà tí a gbà gbé e kalẹ̀.
IṢẸ́ ÀYÀNFÚNNI NO. 4: Ìṣẹ́jú 5. Nígbà tí a bá gbé iṣẹ́ àyànfúnni yìí karí “Àwọn Àkòrí Ọ̀rọ̀ Bíbélì fún Ìjíròrò” gẹ́gẹ́ bí ó ṣe wà nínú Ìtumọ̀ Ayé Tuntun, a óò yàn án fún arákùnrin tàbí arábìnrin. Nígbà tí a bá gbé e karí ìwé Ayọ̀ Ìdílé, a óò yàn án fún arákùnrin. Fún iṣẹ́ àyànfúnni kọ̀ọ̀kan a ti pèsè ẹṣin ọ̀rọ̀ sínú ìtòlẹ́sẹẹsẹ yìí. Nígbà tí a bá yan ọ̀rọ̀ àsọyé yìí fún arákùnrin, kí ó sọ ọ́ pẹ̀lú níní àwùjọ inú Gbọ̀ngàn Ìjọba lọ́kàn. Nígbà tí a bá yan apá yìí fún arábìnrin, kí ó sọ ọ́ ní ìbámu pẹ̀lú àlàyé tí a ṣe fún Iṣẹ́ Àyànfúnni No. 3.
*ÀFIKÚN ÌTÒLẸ́SẸẸSẸ BÍBÉLÌ KÍKÀ: A fi èyí sínú àwọn àkámọ́ lẹ́yìn nọ́ńbà orin fún ọ̀sẹ̀ kọ̀ọ̀kan. Nípa títẹ̀ lé ìtòlẹ́sẹẹsẹ yìí, ní kíka nǹkan bí ojú ìwé mẹ́wàá lọ́sẹ̀, a lè ka Bíbélì látòkè délẹ̀ ní ọdún mẹ́ta. A kò gbé apá kankan nínú ìtòlẹ́sẹẹsẹ ilé ẹ̀kọ́ tàbí àtúnyẹ̀wò alákọsílẹ̀ karí àfikún ìtòlẹ́sẹẹsẹ ìwé kíkà yìí.
Ọ̀RỌ̀ ÀKÍYÈSÍ: Fún àfikún ìsọfúnni àti ìtọ́ni lórí ìmọ̀ràn, ìdíwọ̀n àkókò, àtúnyẹ̀wò alákọsílẹ̀, àti mímúra àwọn iṣẹ́ àyànfúnni sílẹ̀, jọ̀wọ́ wo ojú ìwé 3 nínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti October 1996.
ÌTÒLẸ́SẸẸSẸ
Jan. 4 Bíbélì kíkà: Ìṣípayá 16 sí 18
Orin 23 [*2 Àwọn Ọba 16 sí 19]
No. 1: Bí Ọlọ́run Ṣe Mí Sí Bíbélì (w97-YR 6/15 ojú ìwé 4 sí 8)
No. 2: Ìṣípayá 16:1-16
No. 3: Dáàbò Bo Ọmọ Rẹ Lọ́wọ́ Ìpalára (fy-YR ojú ìwé 61 sí 63 ìpínrọ̀ 24 sí 28)
No. 4: td-YR 13B Ipá Ìwàláàyè Ènìyàn àti ti Ẹranko Ni A Ń Pè Ní Ẹ̀mí
Jan. 11 Bíbélì kíkà: Ìṣípayá 19 sí 22
Orin 126 [*2 Àwọn Ọba 20 sí 25]
No. 1: w91-YR 5/1 ojú ìwé 22 ìpínrọ̀ 5 sí ojú ìwé 23
No. 2: Ìṣípayá 22:1-15
No. 3: Ẹ̀yin Òbí—Ẹ Mú Kí Ọ̀nà Ìjùmọ̀sọ̀rọ̀ Wà Ní Ṣíṣí Sílẹ̀ (fy-YR ojú ìwé 64 sí 66 ìpínrọ̀ 1 sí 7)
No. 4: td-YR 13D Ìdí Tí Àwọn Kristẹni Tòótọ́ Fi Ń Kọ Onírúurú Ìbẹ́mìílò Sílẹ̀
Jan. 18 Bíbélì kíkà: Jẹ́nẹ́sísì 1 sí 3
Orin 84 [*1 Kíróníkà 1 sí 6]
No. 1: w83-YR 7/15 ojú ìwé 12 sí ojú ìwé 14 ìpínrọ̀ 1
No. 2: Jẹ́nẹ́sísì 1:1-13
No. 3: Fi Ìjẹ́pàtàkì Ìwà Rere àti Ohun Tẹ̀mí Kọ́ Àwọn Ọmọ (fy-YR ojú ìwé 67 sí 70 ìpínrọ̀ 8 sí 14)
No. 4: td-YR 36A Jèhófà Ọlọ́run Wa Jẹ́ Jèhófà Kan Ṣoṣo
Jan. 25 Bíbélì kíkà: Jẹ́nẹ́sísì 4 sí 6
Orin 66 [*1 Kíróníkà 7 sí 13]
No. 1: Ṣọ́ra fún Níní Èrò Òdì Síni (w97-YR 5/15 ojú ìwé 26 sí 29)
No. 2: Jẹ́nẹ́sísì 4:1-16
No. 3: Ìdí Tí Ìbáwí àti Ọ̀wọ̀ Fi Ṣe Pàtàkì (fy-YR ojú ìwé 71 àti 72 ìpínrọ̀ 15 sí 18)
No. 4: td-YR 36B Baba Tóbi Ju Ọmọ
Feb. 1 Bíbélì kíkà: Jẹ́nẹ́sísì 7 sí 9
Orin 108 [*1 Kíróníkà 14 sí 21]
No. 1: Òtítọ́ Ni Ohun Tí Bíbélì Sọ Nípa Ìkún Omi (g97-YR 2/8 ojú ìwé 26 àti 27)
No. 2: Jẹ́nẹ́sísì 7:1-16
No. 3: Fi Ojú Ìwòye Ọlọ́run Nípa Iṣẹ́ àti Eré Kọ́ Àwọn Ọmọ (fy-YR ojú ìwé 72 sí 75 ìpínrọ̀ 19 sí 25)
No. 4: td-YR 36D Bí Ọlọ́run àti Kristi Ṣe Jẹ́ Ọ̀kan
Feb. 8 Bíbélì kíkà: Jẹ́nẹ́sísì 10 sí 12
Orin 132 [*1 Kíróníkà 22 sí 29]
No. 1: Ohun Tí Ó Jẹ́ Òtítọ́ Nípa Irọ́ Pípa (g97-YR 2/22 ojú ìwé 17 sí 19)
No. 2: Jẹ́nẹ́sísì 12:1-20
No. 3: Ọ̀tẹ̀ Ọmọdé àti Ohun Tí Ó Ń Fà Á (fy-YR ojú ìwé 76 sí 79 ìpínrọ̀ 1 sí 8)
No. 4: td-YR 36E Ẹ̀mí Mímọ́ Jẹ́ Ipá Ìṣiṣẹ́ Ọlọ́run
Feb. 15 Bíbélì kíkà: Jẹ́nẹ́sísì 13 sí 15
Orin 49 [*2 Kíróníkà 1 sí 8]
No. 1: Àìlera Ẹ̀dá Ènìyàn Ń Fi Hàn Pé Agbára Jèhófà Pọ̀ (w97-YR 6/1 ojú ìwé 24 sí 27)
No. 2: Jẹ́nẹ́sísì 14:8-20
No. 3: td-YR 31A Kì Í Ṣe Jèhófà Ni Ó Ń Fa Àwọn Ìṣòro Ayé
No. 4: Má Ṣe Gbọ̀jẹ̀gẹ́ Tàbí Kí O Le Koko Jù (fy-YR ojú ìwé 80 àti 81 ìpínrọ̀ 10 sí 13)
Feb. 22 Bíbélì kíkà: Jẹ́nẹ́sísì 16 sí 19
Orin 188 [*2 Kíróníkà 9 sí 17]
No. 1: Ohun Tí Àdúrà Rẹ Fi Hàn (w97-YR 7/1 ojú ìwé 27 sí 30)
No. 2: Jẹ́nẹ́sísì 18:1-15
No. 3: Kíkúnjú Àwọn Àìní Pàtàkì Tí Ọmọ Rẹ Ní Lè Dènà Ọ̀tẹ̀ (fy-YR ojú ìwé 82 sí 84 ìpínrọ̀ 14 sí 18)
No. 4: td-YR 31B Ìdí Tí Ọlọ́run Fi Fàyè Gba Ìwà Burúkú
Mar. 1 Bíbélì kíkà: Jẹ́nẹ́sísì 20 sí 23
Orin 54 [*2 Kíróníkà 18 sí 24]
No. 1: Bí O Ṣe Lè Kọ́ Ẹ̀rí Ọkàn Rẹ Lẹ́kọ̀ọ́ (w97-YR 8/1 ojú ìwé 4 sí 6)
No. 2: Jẹ́nẹ́sísì 23:1-13
No. 3: td-YR 31D Jàǹfààní Láti Inú Àánú Ọlọ́run
No. 4: Àwọn Ọ̀nà Tí A Lè Gba Ran Ọmọ kan Tí Ó Ṣàṣìṣe Lọ́wọ́ (fy-YR ojú ìwé 85 sí 87 ìpínrọ̀ 19 sí 23)
Mar. 8 Bíbélì kíkà: Jẹ́nẹ́sísì 24 àti 25
Orin 121 [*2 Kíróníkà 25 sí 31]
No. 1: Òtítọ́ Ń Dáni Sílẹ̀ Lómìnira Kúrò Lọ́wọ́ Kí Ni? (w97-YR 2/1 ojú ìwé 4 sí 7)
No. 2: Jẹ́nẹ́sísì 24:1-4, 10-21
No. 3: td-YR 31E Ìjọba Ọlọ́run Ni Ìrètí Kan Ṣoṣo Tí Ènìyàn Ní
No. 4: Bíbá Ọlọ̀tẹ̀ Paraku Lò (fy-YR ojú ìwé 87 sí 89 ìpínrọ̀ 24 sí 27)
Mar. 15 Bíbélì kíkà: Jẹ́nẹ́sísì 26 sí 28
Orin 197 [*2 Kíróníkà 32 sí 36]
No. 1: Àyè Orin Nínú Ìjọsìn Òde Òní (w97-YR 2/1 ojú ìwé 24 sí 28)
No. 2: Jẹ́nẹ́sísì 26:1-14
No. 3: Dáàbo Bo Ìdílé Rẹ Lọ́wọ́ Agbára Ìdarí Apanirun (fy-YR ojú ìwé 90 sí 92 ìpínrọ̀ 1 sí 7)
No. 4: td-YR 20A Gbogbo Kristẹni Tòótọ́ Gbọ́dọ̀ Jẹ́ Ẹlẹ́rìí
Mar. 22 Bíbélì kíkà: Jẹ́nẹ́sísì 29 sí 31
Orin 4 [*Ẹ́sírà 1 sí 7]
No. 1: Ilẹ̀ Ayé Kì Yóò Jóná Lúúlúú (g97-YR 1/8 ojú ìwé 26 àti 27)
No. 2: Jẹ́nẹ́sísì 31:1-18
No. 3: td-YR 20B Máa Fi Ìtara Jẹ́rìí Lọ
No. 4: Ojú Ìwòye Ọlọ́run Nípa Ìbálòpọ̀ (fy-YR ojú ìwé 92 sí 94 ìpínrọ̀ 8 sí 13)
Mar. 29 Bíbélì kíkà: Jẹ́nẹ́sísì 32 sí 35
Orin 143 [*Ẹ́sírà 8 sí Nehemáyà 4]
No. 1: Ìwòsàn Ìyanu Láti Ọ̀dọ̀ Ọlọ́run—Nígbà Wo? (w97-YR 7/1 ojú ìwé 4 sí 7)
No. 2: Jẹ́nẹ́sísì 35:1-15
No. 3: Ran Àwọn Ọmọ Rẹ Lọ́wọ́ Láti Yan Ọ̀rẹ́ Rere (fy-YR ojú ìwé 95 àti 96 ìpínrọ̀ 14 sí 18)
No. 4: td-YR 20D Bọ́ Lọ́wọ́ Ẹ̀jẹ̀ Gbogbo Ènìyàn
Apr. 5 Bíbélì kíkà: Jẹ́nẹ́sísì 36 sí 38
Orin 106 [*Nehemáyà 5 sí 11]
No. 1: Ìgbàlà—Ohun Tí Ó Túmọ̀ Sí Gan-an (w97-YR 8/15 ojú ìwé 4 sí 7)
No. 2: Jẹ́nẹ́sísì 38:6-19, 24-26
No. 3: td-YR 22A Ìdí Tí Ọlọ́run Kò Fi Tẹ́wọ́ Gba Ìjọsìn Àwọn Baba Ńlá
No. 4: Yíyan Eré Ìnàjú Tí Ó Gbámúṣé fún Ìdílé (fy-YR ojú ìwé 97 sí 102 ìpínrọ̀ 19 sí 27)
Apr. 12 Bíbélì kíkà: Jẹ́nẹ́sísì 39 sí 41
Orin 34 [*Nehemáyà 12 sí Ẹ́sítérì 5]
No. 1: Èé Ṣe Tí Ó Fi Yẹ Kí O Fẹjọ́ Ẹni Tí Ó Hùwà Ibi Sùn? (w97-YR 8/15 ojú ìwé 26 sí 29)
No. 2: Jẹ́nẹ́sísì 40:1-15
No. 3: Ìjìnlẹ̀ Òye Láti Inú Ìwé Mímọ́ fún Àwọn Ìdílé Olóbìí Anìkàntọ́mọ (fy-YR ojú ìwé 103 sí 105 ìpínrọ̀ 1 sí 8)
No. 4: td-YR 22B Jèhófà Nìkan Ni A Gbọ́dọ̀ Jọ́sìn
Apr. 19 Bíbélì kíkà: Jẹ́nẹ́sísì 42 sí 44
Orin 124 [*Ẹ́sítérì 6 sí Jóòbù 5]
No. 1: Ìdí Tí Ó Fi Yẹ Kí A Ṣàkóso Ìbínú (g97-YR 6/8 ojú ìwé 18 àti 19)
No. 2: Jẹ́nẹ́sísì 42:1-17
No. 3: Ìṣòro Gbígbọ́ Bùkátà Gẹ́gẹ́ Bí Òbí Anìkàntọ́mọ (fy-YR ojú ìwé 105 sí 107 ìpínrọ̀ 9 sí 12)
No. 4: td-YR 4A Amágẹ́dọ́nì Ni Ogun Ọlọ́run Láti Fi Òpin sí Ìwà Burúkú
Apr. 26 Àtúnyẹ̀wò Alákọsílẹ̀. Parí Ìṣípayá 16 sí Jẹ́nẹ́sísì 44
Orin 18 [*Jóòbù 6 sí 14]
May 3 Bíbélì kíkà: Jẹ́nẹ́sísì 45 sí 47
Orin 90 [*Jóòbù 15 sí 23]
No. 1: Àwọn Àjọ̀dún Ìkórè Ha Dùn Mọ́ Ọlọ́run Nínú Bí? (w97-YR 9/15 ojú ìwé 8 àti 9)
No. 2: Jẹ́nẹ́sísì 45:16 sí 46:4
No. 3: Pípèsè Ìbáwí Nínú Ilé Òbí Anìkàntọ́mọ (fy-YR ojú ìwé 107 sí 109 ìpínrọ̀ 13 sí 17)
No. 4: td-YR 4B Amágẹ́dọ́nì Kì Yóò Rú Òfin Ìfẹ́ Ọlọ́run
May 10 Bíbélì kíkà: Jẹ́nẹ́sísì 48 sí 50
Orin 76 [*Jóòbù 24 sí 33]
No. 1: w83-YR 7/15 ojú ìwé 14 ìpínrọ̀ 2 sí ojú ìwé 15
No. 2: Jẹ́nẹ́sísì 49:13-28
No. 3: Ṣíṣẹ́gun Ìdánìkanwà (fy-YR ojú ìwé 110 sí 113 ìpínrọ̀ 18 sí 22)
No. 4: td-YR 17A Ìbatisí Jẹ́ Ohun kan Tí A Ń Béèrè Lọ́wọ́ Kristẹni
May 17 Bíbélì kíkà: Ẹ́kísódù 1 sí 4
Orin 2 [*Jóòbù 34 sí 42]
No. 1: w83-YR 10/15 ojú ìwé 25 sí ojú ìwé 26 ìpínrọ̀ 6
No. 2: Ẹ́kísódù 4:1-17
No. 3: td-YR 17B Ìbatisí Kò Wẹ Ẹ̀ṣẹ̀ Nù
No. 4: Bí A Ṣe Lè Ṣèrànwọ́ fún Àwọn Ìdílé Olóbìí Anìkàntọ́mọ (fy-YR ojú ìwé 113 sí 115 ìpínrọ̀ 23 sí 27)
May 24 Bíbélì kíkà: Ẹ́kísódù 5 sí 8
Orin 42 [*Sáàmù 1 sí 17]
No. 1: Wọ́n Tòṣì Síbẹ̀ Wọ́n Lọ́rọ̀—Báwo Ni Ó Ṣe Lè Rí Bẹ́ẹ̀? (w97-YR 9/15 ojú ìwé 3 sí 7)
No. 2: Ẹ́kísódù 7:1-13
No. 3: td-YR 8A Ọlọ́run Ni Ó Mí Sí Bíbélì
No. 4: Àwọn Àǹfààní Fífi Ìṣarasíhùwà Bí Ti Ọlọ́run Kojú Àìsàn (fy-YR ojú ìwé 116 sí 119 ìpínrọ̀ 1 sí 9)
May 31 Bíbélì kíkà: Ẹ́kísódù 9 sí 12
Orin 24 [*Sáàmù 18 sí 28]
No. 1: Ohun Tí Ó Túmọ̀ Sí Láti Má Ṣe Jẹ́ Apá Kan Ayé (g97-YR 9/8 ojú ìwé 12 àti 13)
No. 2: Ẹ́kísódù 12:21-36
No. 3: Ìníyelórí Ẹ̀mí Tí Ń Woni Sàn (fy-YR ojú ìwé 120 àti 121 ìpínrọ̀ 10 sí 13)
No. 4: td-YR 8B Bíbélì Wúlò fún Ọjọ́ Wa
June 7 Bíbélì kíkà: Ẹ́kísódù 13 sí 16
Orin 58 [*Sáàmù 29 sí 38]
No. 1: Bí A Ṣe Lè Rí Ìrètí Nínú Àìsírètí (w97-YR 5/15 ojú ìwé 22 sí 25)
No. 2: Ẹ́kísódù 15:1-13
No. 3: Gbé Àwọn Ohun Àkọ́múṣe Kalẹ̀ sì Ran Àwọn Ọmọ Lọ́wọ́ Láti Kojú Àìsàn Nínú Ìdílé (fy-YR ojú ìwé 122 àti 123 ìpínrọ̀ 14 sí 18)
No. 4: td-YR 8D Bíbélì Jẹ́ Ìwé Tí Ó Wà fún Gbogbo Aráyé
June 14 Bíbélì kíkà: Ẹ́kísódù 17 sí 20
Orin 115 [*Sáàmù 39 sí 50]
No. 1: Bí Àwọn Kristẹni Ṣe Ń Bọlá fún Àwọn Òbí Àgbàlagbà (w97-YR 9/1 ojú ìwé 4 sí 7)
No. 2: Ẹ́kísódù 17:1-13
No. 3: td-YR 11A Ìdí Tí Àwọn Kristẹni Fi Gbọ́dọ̀ Yẹra fún Ẹ̀jẹ̀
No. 4: Ojú Tí Ó Yẹ Kí A Fi Wo Ìtọ́jú Ìṣègùn (fy-YR ojú ìwé 124 sí 127 ìpínrọ̀ 19 sí 23)
June 21 Bíbélì kíkà: Ẹ́kísódù 21 sí 24
Orin 5 [*Sáàmù 51 sí 65]
No. 1: Ìmọ̀ Ìjìnlẹ̀ Tòótọ́ àti Bíbélì Fohùn Ṣọ̀kan (g97-YR 7/8 ojú ìwé 26 àti 27)
No. 2: Ẹ́kísódù 21:1-15
No. 3: Báwo Ni Aya Tí Ó Jẹ́ Onígbàgbọ́ Ṣe Lè Mú Kí Àlàáfíà Jọba Nínú Ìdílé Tí Ó Pínyà? (fy-YR ojú ìwé 128 sí 132 ìpínrọ̀ 1 sí 9)
No. 4: td-YR 11B Ìgbọràn sí Ọlọ́run Ni Àkọ́kọ́ fún Àwọn Kristẹni
June 28 Bíbélì kíkà: Ẹ́kísódù 25 sí 28
Orin 47 [*Sáàmù 66 sí 74]
No. 1: Mọ Jèhófà, Ọlọ́run Náà Tí Ó Jẹ́ Ẹni Gidi (w97-YR 10/1 ojú ìwé 4 sí 8)
No. 2: Ẹ́kísódù 25:17-30
No. 3: td-YR 30A Àwọn Ìgbà Kèfèrí Dópin ní 1914
No. 4: Báwo Ni Ọkọ Tí Ó Jẹ́ Onígbàgbọ́ Ṣe Lè Mú Kí Àlàáfíà Jọba Nínú Ìdílé Tí Ó Pínyà? (fy-YR ojú ìwé 132 àti 133 ìpínrọ̀ 10 àti 11)
July 5 Bíbélì kíkà: Ẹ́kísódù 29 sí 32
Orin 174 [*Sáàmù 75 sí 85]
No. 1: Má Ṣe Jẹ́ Kí Ẹ̀mí Ayé Bà Ọ́ Jẹ́ (w97-YR 10/1 ojú ìwé 25 sí 29)
No. 2: Ẹ́kísódù 29:1-14
No. 3: Fífi Ìwé Mímọ́ Tọ́ Àwọn Ọmọ Nínú Ìdílé Tí Ó Pínyà (fy-YR ojú ìwé 133 àti 134 ìpínrọ̀ 12 sí 15)
No. 4: td-YR 43A Ṣọ́ọ̀ṣì Tòótọ́ ti Kristi
July 12 Bíbélì kíkà: Ẹ́kísódù 33 sí 36
Orin 214 [*Sáàmù 86 sí 97]
No. 1: Jẹ́ Ẹni Tí Ó Ṣeé Gbẹ́kẹ̀ Lé Kí O sì Pa Ìwà Títọ́ Rẹ Mọ́ (w97-YR 5/1 ojú ìwé 4 sí 7)
No. 2: Ẹ́kísódù 34:17-28
No. 3: Níní Ipò Ìbátan Alálàáfíà Pẹ̀lú Àwọn Òbí Tí Ìsìn Wọn Yàtọ̀ (fy-YR ojú ìwé 134 àti 135 ìpínrọ̀ 16 sí 19)
No. 4: td-YR 43B Orí Kristi Ni A Kọ́ Ṣọ́ọ̀ṣì Kristẹni Sí
July 19 Bíbélì kíkà: Ẹ́kísódù 37 sí 40
Orin 38 [*Sáàmù 98 sí 106]
No. 1: w83-YR 10/15 ojú ìwé 26 ìpínrọ̀ 7 sí ojú ìwé 28
No. 2: Ẹ́kísódù 40:1-16
No. 3: Ìpèníjà Jíjẹ́ Òbí Nínú Ìgbéyàwó Àtúnṣe (fy-YR ojú ìwé 136 sí 139 ìpínrọ̀ 20 sí 25)
No. 4: td-YR 29A Ìmọ̀ Sáyẹ́ǹsì Tòótọ́ àti Ìṣẹ̀dá Fohùn Ṣọ̀kan
July 26 Bíbélì kíkà: Léfítíkù 1 sí 4
Orin 26 [*Sáàmù 107 sí 118]
No. 1: w84-YR 2/15 ojú ìwé 24 sí ojú ìwé 26 ìpínrọ̀ 1
No. 2: Léfítíkù 2:1-13
No. 3: Má Ṣe Jẹ́ Kí Ìlépa Ọrọ̀ Àlùmọ́nì Pín Ìdílé Rẹ Níyà (fy-YR ojú ìwé 140 sí 141 ìpínrọ̀ 26 sí 28)
No. 4: td-YR 29B Gígùn Àwọn Ọjọ́ Ìṣẹ̀dá Ha Jẹ́ Wákàtí Mẹ́rìnlélógún Bí?
Aug. 2 Bíbélì kíkà: Léfítíkù 5 sí 7
Orin 9 [*Sáàmù 119 sí 125]
No. 1: Àṣírí Ayọ̀ Tòótọ́ (w97-YR 10/15 ojú ìwé 5 sí 7)
No. 2: Léfítíkù 6:1-13
No. 3: Àwọn Ọṣẹ́ Tí Ìmukúmu Ń Ṣe (fy-YR ojú ìwé 142 àti 143 ìpínrọ̀ 1 sí 4)
No. 4: td-YR 2A Ṣé Orí Àgbélébùú Ni Jésù Ti Kú?
Aug. 9 Bíbélì kíkà: Léfítíkù 8 sí 10
Orin 210 [*Sáàmù 126 sí 143]
No. 1: Fífòyemọ Ìlànà Ń Fi Hàn Pé A Dàgbà Dénú (w97-YR 10/15 ojú ìwé 28 sí 30)
No. 2: Léfítíkù 10:12-20
No. 3: Ríran Mẹ́ńbà Ìdílé Tí Ó Jẹ́ Onímukúmu Lọ́wọ́ (fy-YR ojú ìwé 143 sí 147 ìpínrọ̀ 5 sí 13)
No. 4: td-YR 2B Ìdí Tí Ọlọ́run Kò Fi Tẹ́wọ́ Gba Lílo Àgbélébùú Nínú Ìjọsìn
Aug. 16 Bíbélì kíkà: Léfítíkù 11 sí 13
No. 1: Ṣọ́ra fún ‘Àwọn Epikúréì’ (w97-YR 11/1 ojú ìwé 23 sí 25)
No. 2: Léfítíkù 13:1-17
No. 3: Ìwà Ipá Abẹ́lé àti Bí A Ṣe Lè Yẹra Fun Un (fy-YR ojú ìwé 147 sí 149 ìpínrọ̀ 14 sí 22)
No. 4: td-YR 24A Èé Ṣe Tí Àwọn Ènìyàn Fi Ń Kú?
Aug. 23 Bíbélì kíkà: Léfítíkù 14 àti 15
Orin 137 [*Òwe 6 sí 14]
No. 1: Àwọn Ọjọ́ Ìkẹyìn Nìyí Ní Ti Gidi (w97-YR 4/1 ojú ìwé 4 sí 8)
No. 2: Léfítíkù 14:33-47
No. 3: td-YR 24B Ipò Wo Ni Àwọn Òkú Wà?
No. 4: Ṣé Ìpínyà Ni Ojútùú Rẹ̀? (fy-YR ojú ìwé 150 sí 152 ìpínrọ̀ 23 sí 26)
Aug. 30 Àtúnyẹ̀wò Alákọsílẹ̀. Parí Jẹ́nẹ́sísì 45 sí Léfítíkù 15
Orin 145 [*Òwe 15 sí 22]
Sept. 6 Bíbélì kíkà: Léfítíkù 16 sí 18
Orin 222 [*Òwe 23 sí 31]
No. 1: Ìgbà Tí Ìyà Kò Ní Sí Mọ́ (w97-YR 2/15 ojú ìwé 4 sí 7)
No. 2: Léfítíkù 16:20-31
No. 3: td-YR 24D Ìdí Tí Kò Fi Ṣeé Ṣe Láti Bá Òkú Sọ̀rọ̀
No. 4: Bí A Ṣe Lè Yanjú Ìṣòro Ìgbéyàwó Lọ́nà Ti Ìwé Mímọ́ (fy-YR ojú ìwé 153 sí 156 ìpínrọ̀ 1 sí 9)
Sept. 13 Bíbélì kíkà: Léfítíkù 19 sí 21
Orin 122 [*Oníwàásù 1 sí 12]
No. 1: Ìdí Tí Ìṣẹ́ra-Ẹni-Níṣẹ̀ẹ́ Kò Fi Lè Jẹ́ Ọ̀nà Àtilọ́gbọ́n (g97-YR 10/8 ojú ìwé 20 àti 21)
No. 2: Léfítíkù 19:16-18, 26-37
No. 3: td-YR 10A Ta Ni Èṣù, Ibo Ni Ó sì Ti Wá?
No. 4: Fífi Ẹ̀tọ́ Ìgbéyàwó Fúnni (fy-YR ojú ìwé 156 sí 158 ìpínrọ̀ 10 sí 13)
Sept. 20 Bíbélì kíkà: Léfítíkù 22 sí 24
Orin 8 [*Orin Sólómọ́nì 1 sí Aísáyà 5]
No. 1: Ǹjẹ́ Gbogbo Àròyé Ni Ó Burú? (w97-YR 12/1 ojú ìwé 29 sí 31)
No. 2: Léfítíkù 23:15-25
No. 3: td-YR 10B Èṣù Ni Ẹni Tí A Kò Lè Rí Tí Ń Ṣàkóso Ayé
No. 4: Àwọn Ìpìlẹ̀ Tí Bíbélì Fọwọ́ Sí Fún Ìkọ̀sílẹ̀ (fy-YR ojú ìwé 158 àti 159 ìpínrọ̀ 14 sí 16)
Sept. 27 Bíbélì kíkà: Léfítíkù 25 sí 27
Orin 120 [*Aísáyà 6 sí 14]
No. 1: w84-YR 2/15 ojú ìwé 26 ìpínrọ̀ 2 àti ojú ìwé 27
No. 2: Léfítíkù 25:13-28
No. 3: td-YR 10D Àwọn Wo Ni Ẹ̀mí Èṣù?
No. 4: Ohun Tí Ìwé Mímọ́ Sọ Nípa Ìpínyà (fy-YR ojú ìwé 160 sí 162 ìpínrọ̀ 17 sí 22)
Oct. 4 Bíbélì kíkà: Númérì 1 sí 3
Orin 30 [*Aísáyà 15 sí 25]
No. 1: w84-YR 4/15 ojú ìwé 28 sí ojú ìwé 30 ìpínrọ̀ 2
No. 2: Númérì 1:44-54
No. 3: Dídàgbà Pọ̀ (fy-YR ojú ìwé 163 sí 165 ìpínrọ̀ 1 sí 9)
No. 4: td-YR 25A Kí Ni Ète Ọlọ́run fún Ilẹ̀ Ayé?
Oct. 11 Bíbélì kíkà: Númérì 4 sí 6
Orin 97 [*Aísáyà 26 sí 33]
No. 1: Jèhófà Ń Fi Ìyọ́nú Ṣàkóso (w97-YR 12/15 ojú ìwé 28 àti 29)
No. 2: Númérì 4:17-33
No. 3: Fífún Ìdè Ìgbéyàwó Lókun Lẹ́ẹ̀kan Sí I (fy-YR ojú ìwé 166 àti 167 ìpínrọ̀ 10 sí 13)
No. 4: td-YR 25B A Kì Yóò Pa Ilẹ̀ Ayé Run Láé
Oct. 18 Bíbélì kíkà: Númérì 7 sí 9
Orin 96 [*Aísáyà 34 sí 41]
No. 1: Ibi Tí A Ti Lè Rí Ayọ̀ Tòótọ́ (w97-YR 3/15 ojú ìwé 23)
No. 2: Númérì 9:1-14
No. 3: Gbádùn Àwọn Ọmọ-Ọmọ Rẹ Kí O sì Yíwọ́ Padà Bí O Ti Ń Darúgbó (fy-YR ojú ìwé 168 sí 170 ìpínrọ̀ 14 sí 19)
No. 4: td-YR 44A Àwọn Wòlíì Èké Kì Í Ṣe Ohun Tuntun
Oct. 25 Bíbélì kíkà: Númérì 10 sí 12
Orin 125 [*Aísáyà 42 sí 49]
No. 1: Jèhófà Ń Bìkítà fún Àwọn Tí A Ń Pọ́n Lójú (w97-YR 4/15 ojú ìwé 4 sí 7)
No. 2: Númérì 10:11-13, 29-36
No. 3: Kíkojú Àdánù Alábàáṣègbéyàwó Rẹ (fy-YR ojú ìwé 170 sí 172 ìpínrọ̀ 20 sí 25)
No. 4: td-YR 32A Ìdí Tí Ìwòsàn Tẹ̀mí Fi Ṣe Pàtàkì Gan-an
Nov. 1 Bíbélì kíkà: Númérì 13 sí 15
Orin 64 [*Aísáyà 50 sí 58]
No. 1: Ìdí Tí Iṣẹ́ Ìyanu Nìkan Kò Fi Gbé Ìgbàgbọ́ Ró (w97-YR 3/15 ojú ìwé 4 sí 7)
No. 2: Númérì 14:13-25
No. 3: td-YR 32B Ìjọba Ọlọ́run Yóò Mú Ìwòsàn Ti Ara Wíwàpẹ́títí Wá
No. 4: Bí Àwọn Kristẹni Ṣe Ń Bọlá fún Àwọn Òbí Wọn Àgbà (fy-YR ojú ìwé 173 sí 175 ìpínrọ̀ 1 sí 5)
Nov. 8 Bíbélì kíkà: Númérì 16 sí 19
Orin 78 [*Aísáyà 59 sí 66]
No. 1: Ìdí Tí Ipò Òṣì Kò Fi Dá Olè Jíjà Láre (g97-YR 11/8 ojú ìwé 18 àti 19)
No. 2: Númérì 18:1-14
No. 3: Fi Ìfẹ́ àti Ẹ̀mí Ìfọ̀ràn-Rora-Ẹni-Wò Hàn (fy-YR ojú ìwé 175 sí 178 ìpínrọ̀ 6 sí 14)
No. 4: td-YR 32D Ìgbàgbọ́ Wò-Ó-Sàn Òde Òní Kò Wá Láti Ọ̀dọ̀ Jèhófà
Nov. 15 Bíbélì kíkà: Númérì 20 sí 22
Orin 46 [*Jeremáyà 1 sí 6]
No. 1: Bí Bíbélì Ṣe Tẹ̀ Wá Lọ́wọ́—Apá Kìíní (w97-YR 8/15 ojú ìwé 8 sí 11)
No. 2: Númérì 20:14-26
No. 3: Máa Wojú Jèhófà fún Okun Nígbà Gbogbo (fy-YR ojú ìwé 179 sí 182 ìpínrọ̀ 15 sí 21)
No. 4: td-YR 32E Sísọ̀rọ̀ Ní Àwọn Ahọ́n Àjèjì Jẹ́ Ìpèsè Onígbà Kúkúrú
Nov. 22 Bíbélì kíkà: Númérì 23 sí 26
Orin 59 [*Jeremáyà 7 sí 13]
No. 1: Bí Bíbélì Ṣe Tẹ̀ Wá Lọ́wọ́—Apá Kejì (w97-YR 9/15 ojú ìwé 25 sí 29)
No. 2: Númérì 23:1-12
No. 3: Mú Ìfọkànsin Ọlọ́run àti Ìkóra-Ẹni-Níjàánu Dàgbà (fy-YR ojú ìwé 183 àti 184 ìpínrọ̀ 1 sí 5)
No. 4: td-YR 41A Kìkì 144,000 Ní Ń Lọ Sí Ọ̀run
Nov. 29 Bíbélì kíkà: Númérì 27 sí 30
Orin 180 [*Jeremáyà 14 sí 21]
No. 1: Bí Bíbélì Ṣe Tẹ̀ Wá Lọ́wọ́—Apá Kẹta (w97-YR 10/15 ojú ìwé 8 sí 12)
No. 2: Númérì 27:1-11
No. 3: Ojú Ìwòye Tí Ó Tọ́ Nípa Ipò Orí (fy-YR ojú ìwé 185 àti 186 ìpínrọ̀ 6 sí 9)
No. 4: td-YR 16A Hẹ́ẹ̀lì Kì Í Ṣe Ibi Tí A Ti Ń Fi Iná Dáni Lóró
Dec. 6 Bíbélì kíkà: Númérì 31 àti 32
Orin 170 [*Jeremáyà 22 sí 28]
No. 1: Orísun Kérésìmesì Òde Òní (w97-YR 12/15 ojú ìwé 4 sí 7)
No. 2: Númérì 31:13-24
No. 3: Ipa Pàtàkì Tí Ìfẹ́ Ń Kó Nínú Ìdílé (fy-YR ojú ìwé 186 àti 187 ìpínrọ̀ 10 sí 12)
No. 4: td-YR 16B Iná Ṣàpẹẹrẹ Ìparun Yán-án Yán-án
Dec. 13 Bíbélì kíkà: Númérì 33 sí 36
Orin 51 [*Jeremáyà 29 sí 34]
No. 1: w84-YR 4/15 ojú ìwé 30 ìpínrọ̀ 3 àti ojú ìwé 31
No. 2: Númérì 36:1-13
No. 3: td-YR 16D Ìròyìn Nípa Ọlọ́rọ̀ àti Lásárù—Kì Í Ṣe Ẹ̀rí Ìdálóró Ayérayé
No. 4: Ṣíṣe Ìfẹ́ Ọlọ́run Gẹ́gẹ́ Bí Ìdílé (fy-YR ojú ìwé 188 àti 189 ìpínrọ̀ 13 sí 15)
Dec. 20 Bíbélì kíkà: Diutarónómì 1 sí 3
Orin 159 [*Jeremáyà 35 sí 41]
No. 1: w84-YR 8/15 ojú ìwé 27 àti 28 ìpínrọ̀ 5
No. 2: Diutarónómì 2:1-15
No. 3: td-YR 38A Àwọn Kristẹni Ìjímìjí Kò ṣe Ọjọ́ Ìbí Tàbí Kérésìmesì
No. 4: Ìdílé àti Ọjọ́ Ọ̀la Rẹ (fy-YR ojú ìwé 190 àti 191 ìpínrọ̀ 16 sí 18)
Dec. 27 Àtúnyẹ̀wò Alákọsílẹ̀. Parí Léfítíkù 16 sí Diutarónómì 3
Orin 192 [*Jeremáyà 42 sí 48]