ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • nwt Kólósè 1:1-4:18
  • Kólósè

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Kólósè
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
Kólósè

SÍ ÀWỌN ARÁ KÓLÓSÈ

1 Pọ́ọ̀lù, àpọ́sítélì Kristi Jésù nípa ìfẹ́ Ọlọ́run pẹ̀lú Tímótì+ arákùnrin wa, 2 sí àwọn ẹni mímọ́ àti àwọn arákùnrin olóòótọ́ nínú Kristi ní Kólósè:

Kí ẹ ní inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí àti àlàáfíà látọ̀dọ̀ Ọlọ́run tó jẹ́ Baba wa.

3 Gbogbo ìgbà la máa ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run Baba Olúwa wa Jésù Kristi, nígbà tí a bá ń gbàdúrà fún yín, 4 torí a ti gbọ́ nípa ìgbàgbọ́ tí ẹ ní nínú Kristi Jésù àti ìfẹ́ tí ẹ ní sí gbogbo ẹni mímọ́, 5 nítorí ìrètí tí a fi pa mọ́ dè yín ní ọ̀run.+ Ẹ ti gbọ́ nípa ìrètí yìí tẹ́lẹ̀ nípasẹ̀ ọ̀rọ̀ òtítọ́ tó jẹ́ ìhìn rere 6 tó dé ọ̀dọ̀ yín. Bí ìhìn rere náà ṣe ń so èso, tó sì ń gbilẹ̀ ní gbogbo ayé,+ bẹ́ẹ̀ náà ló ń ṣe láàárín yín láti ọjọ́ tí ẹ ti gbọ́, tí ẹ sì ti mọ inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Ọlọ́run ní òtítọ́ àti lọ́nà tó péye. 7 Ohun tí ẹ ti kọ́ nìyẹn lọ́dọ̀ Épáfírásì+ olùfẹ́, ẹrú ẹlẹgbẹ́ wa, ẹni tó jẹ́ òjíṣẹ́ olóòótọ́ fún Kristi nítorí wa. 8 Ó ti jẹ́ ká gbọ́ nípa ìfẹ́ yín lọ́nà ti ẹ̀mí.*

9 Ìdí nìyẹn tó fi jẹ́ pé, láti ọjọ́ tí a ti gbọ́ nípa rẹ̀, a ò dákẹ́ àdúrà lórí yín,+ a sì ń bẹ̀bẹ̀ pé kí ẹ lè ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìmọ̀ tó péye+ nípa ìfẹ́ Ọlọ́run nínú gbogbo ọgbọ́n àti òye tẹ̀mí,+ 10 kí ẹ lè máa rìn lọ́nà tó yẹ Jèhófà* láti ṣe ìfẹ́ rẹ̀ ní kíkún, bí ẹ ṣe ń so èso nínú gbogbo iṣẹ́ rere, tí ìmọ̀ tó péye tí ẹ ní nípa Ọlọ́run sì ń pọ̀ sí i;+ 11 kí agbára rẹ̀ ológo sì fún yín ní gbogbo agbára tí ẹ nílò,+ kí ẹ lè fara dà á ní kíkún pẹ̀lú sùúrù àti ìdùnnú, 12 bí ẹ ṣe ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Baba tó mú kí ẹ kúnjú ìwọ̀n láti pín nínú ogún àwọn ẹni mímọ́+ nínú ìmọ́lẹ̀.

13 Ó gbà wá lọ́wọ́ àṣẹ òkùnkùn,+ ó sì mú wa lọ sínú ìjọba Ọmọ rẹ̀ ọ̀wọ́n, 14 ẹni tí a tipasẹ̀ rẹ̀ gba ìtúsílẹ̀ nípa ìràpadà, ìyẹn ìdáríjì àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa.+ 15 Òun ni àwòrán Ọlọ́run tí a kò lè rí,+ àkọ́bí nínú gbogbo ẹ̀dá; + 16 nítorí ipasẹ̀ rẹ̀ ni a dá gbogbo ohun mìíràn ní ọ̀run àti ní ayé, àwọn ohun tí a lè rí àti àwọn ohun tí a kò lè rí,+ ì báà jẹ́ ìtẹ́ tàbí ipò olúwa tàbí ìjọba tàbí àṣẹ. Gbogbo ohun mìíràn ni a dá nípasẹ̀ rẹ̀+ àti nítorí rẹ̀. 17 Bákan náà, ó wà ṣáájú gbogbo ohun mìíràn,+ ipasẹ̀ rẹ̀ ni a gbà mú kí gbogbo ohun mìíràn wà, 18 òun sì ni orí fún ara, ìyẹn ìjọ.+ Òun ni ìbẹ̀rẹ̀, àkọ́bí nínú àwọn òkú,+ kí ó lè di ẹni àkọ́kọ́ nínú ohun gbogbo; 19 nítorí ó wu Ọlọ́run láti mú kí ohun gbogbo pé sínú rẹ̀,+ 20 kí ó sì lè tipasẹ̀ rẹ̀ mú gbogbo ohun mìíràn pa dà bá ara rẹ̀ rẹ́,+ ì báà jẹ́ àwọn ohun tó wà ní ayé tàbí àwọn ohun tó wà ní ọ̀run, bí ó ṣe fi ẹ̀jẹ̀ tó ta sílẹ̀ lórí òpó igi oró* mú àlàáfíà wá.+

21 Ní tòótọ́, ẹ̀yin tí ẹ ti di àjèjì àti ọ̀tá nígbà kan rí torí pé àwọn iṣẹ́ burúkú ni èrò yín dá lé, 22 ẹ̀yin ló pa dà mú bá ara rẹ̀ rẹ́ báyìí nípasẹ̀ ẹran ara ẹni tó fi ara rẹ̀ lélẹ̀ fún ikú, kó lè mú yín wá síwájú rẹ̀ ní mímọ́ àti láìní àbààwọ́n àti láìní ẹ̀sùn kankan,+ 23 kìkì pé kí ẹ dúró nínú ìgbàgbọ́,+ kí ẹ fìdí múlẹ̀ lórí ìpìlẹ̀ náà,+ kí ẹ sì fẹsẹ̀ múlẹ̀ ṣinṣin,+ kí ẹ má yà kúrò nínú ìrètí ìhìn rere tí ẹ gbọ́, tí a sì ti wàásù láàárín gbogbo ẹ̀dá tó wà lábẹ́ ọ̀run.+ Torí ìhìn rere yìí la ṣe yan èmi Pọ́ọ̀lù láti di òjíṣẹ́.+

24 Ní báyìí, mò ń yọ̀ nínú ìyà tí mò ń jẹ lórí yín,+ mo sì ń ní ìpọ́njú Kristi tí mi ò tíì ní nínú ẹran ara mi nítorí ara rẹ̀,+ ìyẹn ìjọ.+ 25 Mo di òjíṣẹ́ ìjọ yìí nítorí iṣẹ́ ìríjú+ tí Ọlọ́run fún mi nítorí yín láti wàásù ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ní kíkún, 26 àṣírí mímọ́+ tí a fi pa mọ́ láti àwọn ètò àwọn nǹkan* tó ti kọjá+ àti láti àwọn ìran tó ti kọjá. Àmọ́ ní báyìí, a ti fi han àwọn ẹni mímọ́ rẹ̀,+ 27 ìyẹn àwọn tó wu Ọlọ́run pé kí wọ́n mọ ọrọ̀ ológo nípa àṣírí mímọ́ yìí láàárín àwọn orílẹ̀-èdè,+ àṣírí yìí ni Kristi tó wà ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú yín, ìyẹn ìrètí ògo rẹ̀.+ 28 Òun ni à ń kéde, tí à ń gba gbogbo èèyàn níyànjú nípa rẹ̀, tí a sì ń kọ́ gbogbo èèyàn nínú gbogbo ọgbọ́n, kí a lè mú ẹnì kọ̀ọ̀kan wá ní pípé ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú Kristi.+ 29 Nípa bẹ́ẹ̀, mò ń ṣiṣẹ́ kára, mo sì ń sapá bí agbára rẹ̀ ṣe ń ṣiṣẹ́ gidigidi nínú mi.+

2 Mo fẹ́ kí ẹ mọ bí ìsapá mi ṣe pọ̀ tó lórí yín, lórí àwọn tó wà ní Laodíkíà+ àti lórí gbogbo àwọn tí kò tíì rí mi lójúkojú.* 2 Èyí jẹ́ kí a lè tu ọkàn wọn lára,+ kí a lè so wọ́n pọ̀ di ọ̀kan nínú ìfẹ́,+ kí wọ́n sì lè ní gbogbo ọrọ̀ tó ń wá látinú òye wọn tó dájú hán-ún, kí wọ́n lè ní ìmọ̀ tó péye nípa àṣírí mímọ́ Ọlọ́run, ìyẹn Kristi.+ 3 Inú rẹ̀ ni a fi gbogbo ìṣúra ọgbọ́n àti ti ìmọ̀ pa mọ́ sí.+ 4 Mò ń sọ èyí kí ẹnì kankan má bàa fi ọ̀rọ̀ dídùn tàn yín jẹ. 5 Bí mi ò tiẹ̀ sí lọ́dọ̀ yín nínú ara, mo wà pẹ̀lú yín nínú ẹ̀mí, inú mi ń dùn bí mo ṣe ń rí i pé ẹ wà létòlétò,+ ìgbàgbọ́ yín sì fìdí múlẹ̀ nínú Kristi.+

6 Nítorí náà, bí ẹ ṣe tẹ́wọ́ gba Kristi Jésù Olúwa, ẹ máa rìn ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú rẹ̀, 7 kí ẹ ta gbòǹgbò, kí ẹ sì máa dàgbà nínú rẹ̀,+ kí ẹ fẹsẹ̀ múlẹ̀ nínú ìgbàgbọ́,+ bí a ṣe kọ́ yín, kí ẹ sì máa kún fún ọpẹ́.+

8 Ẹ máa ṣọ́ra kí ẹnikẹ́ni má fi ọgbọ́n orí àti ìtànjẹ lásán+ mú yín lẹ́rú* látinú òfin àtọwọ́dọ́wọ́ èèyàn, nínú àwọn ohun àkọ́bẹ̀rẹ̀ ayé, tí kì í ṣe nínú Kristi; 9 torí pé inú rẹ̀ ni gbogbo ànímọ́* Ọlọ́run pé sí.+ 10 Torí náà, ẹ ti ní ohun gbogbo nípasẹ̀ rẹ̀, ẹni tó jẹ́ orí gbogbo ìjọba àti àṣẹ.+ 11 Àjọṣe tí ẹ ní pẹ̀lú rẹ̀ ti mú kí a dádọ̀dọ́* ẹ̀yin náà pẹ̀lú ìdádọ̀dọ́* tí a kò fi ọwọ́ ṣe nípa bíbọ́ ara ẹ̀ṣẹ̀ kúrò,+ ìyẹn ìdádọ̀dọ́ tó jẹ́ ti Kristi.+ 12 A sin yín pẹ̀lú rẹ̀ nínú ìbatisí rẹ̀,+ àjọṣe tí ẹ sì ní pẹ̀lú rẹ̀ mú kí a gbé ẹ̀yin náà dìde+ pẹ̀lú rẹ̀ nípasẹ̀ ìgbàgbọ́ yín nínú iṣẹ́ agbára Ọlọ́run, ẹni tó gbé e dìde kúrò nínú ikú.+

13 Yàtọ̀ síyẹn, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ ti kú nínú àwọn àṣemáṣe yín àti nínú ipò àìdádọ̀dọ́* ẹran ara yín, Ọlọ́run mú kí ẹ wà láàyè pẹ̀lú rẹ̀.+ Ó dárí gbogbo àṣemáṣe wa jì wá tinútinú,+ 14 ó pa ìwé àfọwọ́kọ rẹ́,*+ èyí tí àwọn àṣẹ wà nínú rẹ̀,+ tó sì lòdì sí wa.+ Ó mú un kúrò lọ́nà bí ó ṣe kàn án mọ́ òpó igi oró.*+ 15 Ó ti tú àwọn alákòóso àti àwọn aláṣẹ sí borokoto, ó fi wọ́n hàn ní gbangba pé a ti ṣẹ́gun wọn,+ ó ń fi òpó igi oró* darí wọn lọ nínú ìjáde àwọn tó ń yọ ayọ̀ ìṣẹ́gun.

16 Nítorí náà, ẹ má ṣe jẹ́ kí ẹnì kankan dá yín lẹ́jọ́ lórí ohun tí ẹ̀ ń jẹ àti ohun tí ẹ̀ ń mu+ tàbí lórí àjọyọ̀ kan tí ẹ ṣe tàbí òṣùpá tuntun+ tàbí sábáàtì.+ 17 Àwọn nǹkan yẹn jẹ́ òjìji àwọn ohun tó ń bọ̀,+ àmọ́ Kristi ni ohun gidi náà.+ 18 Ẹ má ṣe jẹ́ kí ẹnì kankan mú kí ẹ̀bùn náà bọ́ mọ́ yín lọ́wọ́,+ ẹni tó fẹ́ràn ìrẹ̀lẹ̀ tó jẹ́ ẹ̀tàn àti ọ̀nà ìjọsìn àwọn áńgẹ́lì, “tó dúró lórí”* àwọn ohun tó ti rí. Ní tòótọ́, kò sídìí tó fi yẹ kó gbéra ga, àmọ́ ó ṣe bẹ́ẹ̀ torí ó ń ronú lọ́nà ti ara, 19 kò sì di orí náà mú ṣinṣin,+ ipasẹ̀ ẹni tí gbogbo ara fi ń rí ohun tó nílò, tó sì so gbogbo rẹ̀ pọ̀ di ọ̀kan nípasẹ̀ àwọn oríkèé àti àwọn iṣan tó de eegun pọ̀, tó ń mú kó máa dàgbà sókè bí Ọlọ́run ṣe fẹ́.+

20 Bí ẹ bá ti kú pẹ̀lú Kristi nínú àwọn ohun àkọ́bẹ̀rẹ̀ ayé,+ kí ló dé tí ẹ̀ ń gbé ìgbé ayé yín bíi pé ẹ ṣì jẹ́ apá kan ayé bí ẹ ṣe ń fi ara yín sábẹ́ àwọn àṣẹ tó sọ pé:+ 21 “Má dì í mú, má tọ́ ọ wò, má fọwọ́ kàn án,” 22 ní ti gbogbo àwọn nǹkan tó ń ṣègbé lẹ́yìn lílò, gẹ́gẹ́ bí àwọn àṣẹ àti àwọn ẹ̀kọ́ tó wá látọwọ́ èèyàn ṣe sọ?+ 23 Bó tiẹ̀ dà bíi pé àwọn nǹkan yẹn bọ́gbọ́n mu, ṣe ni àwọn tó ń ṣe wọ́n yan ọ̀nà ìjọsìn tiwọn fúnra wọn. Wọ́n ń fìyà jẹ ara wọn+ torí wọ́n fẹ́ kí àwọn èèyàn máa rò pé àwọn nírẹ̀lẹ̀. Àmọ́ àwọn nǹkan yẹn kò ní àǹfààní kankan téèyàn bá fẹ́ borí ìfẹ́ ti ara.

3 Tó bá jẹ́ pé a ti gbé yín dìde pẹ̀lú Kristi,+ ẹ máa wá àwọn nǹkan ti òkè, níbi tí Kristi jókòó sí ní ọwọ́ ọ̀tún Ọlọ́run.+ 2 Ẹ máa ronú nípa àwọn nǹkan ti òkè,+ kì í ṣe nípa àwọn nǹkan ti ayé.+ 3 Nítorí ẹ ti kú, a sì ti fi ìyè yín pa mọ́ sọ́dọ̀ Kristi ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú Ọlọ́run. 4 Nígbà tí a bá fi Kristi, ìyè wa,+ hàn kedere, nígbà náà, a ó fi ẹ̀yin náà hàn kedere pẹ̀lú rẹ̀ nínú ògo.+

5 Nítorí náà, ẹ sọ àwọn ẹ̀yà ara yín+ tó wà láyé di òkú ní ti ìṣekúṣe,* ìwà àìmọ́, ìfẹ́ ìbálòpọ̀ tí kò níjàánu,+ ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ àti ojúkòkòrò, tó jẹ́ ìbọ̀rìṣà. 6 Tìtorí àwọn nǹkan yìí ni ìrunú Ọlọ́run ṣe ń bọ̀. 7 Bí ẹ̀yin náà ṣe ń ṣe* nìyẹn nínú ọ̀nà ìgbésí ayé yín ti tẹ́lẹ̀.*+ 8 Àmọ́ ní báyìí, ẹ gbọ́dọ̀ mú gbogbo wọn kúrò lọ́dọ̀ yín: ìrunú, ìbínú, ìwà burúkú+ àti ọ̀rọ̀ èébú,+ kí ẹ sì mú ọ̀rọ̀ rírùn+ kúrò lẹ́nu yín. 9 Ẹ má ṣe máa parọ́ fún ara yín.+ Ẹ bọ́ ìwà* àtijọ́ sílẹ̀+ pẹ̀lú àwọn àṣà rẹ̀, 10 ẹ sì fi ìwà tuntun wọ ara yín láṣọ,+ èyí tí à ń fi ìmọ̀ tó péye sọ di tuntun, kí ó lè jọ àwòrán Ẹni tó dá a,+ 11 níbi tí kò ti sí Gíríìkì tàbí Júù, ìdádọ̀dọ́* tàbí àìdádọ̀dọ́,* àjèjì, Sítíánì,* ẹrú tàbí òmìnira; àmọ́ Kristi ni ohun gbogbo, ó sì wà nínú ohun gbogbo.+

12 Nítorí náà, gẹ́gẹ́ bí àyànfẹ́ Ọlọ́run,+ ẹ̀yin tí ẹ jẹ́ mímọ́ àti olùfẹ́, ẹ fi ìfẹ́ oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ ti àánú,+ inú rere, ìrẹ̀lẹ̀,*+ ìwà tútù+ àti sùúrù+ wọ ara yín láṣọ. 13 Ẹ máa fara dà á fún ara yín, kí ẹ sì máa dárí ji ara yín fàlàlà,+ kódà tí ẹnikẹ́ni bá ní ìdí láti fẹ̀sùn kan ẹlòmíì.+ Bí Jèhófà* ṣe dárí jì yín ní fàlàlà, ẹ̀yin náà gbọ́dọ̀ máa ṣe bẹ́ẹ̀.+ 14 Àmọ́, yàtọ̀ sí gbogbo àwọn nǹkan yìí, ẹ fi ìfẹ́ wọ ara yín láṣọ,+ nítorí ó jẹ́ ìdè ìrẹ́pọ̀ pípé.+

15 Bákan náà, ẹ jẹ́ kí àlàáfíà Kristi jọba lọ́kàn yín,*+ nítorí a ti pè yín sínú àlàáfíà yẹn nínú ara kan. Torí náà, ẹ máa dúpẹ́. 16 Ẹ jẹ́ kí ọ̀rọ̀ Kristi máa gbé inú yín lọ́pọ̀lọpọ̀ nínú gbogbo ọgbọ́n. Ẹ máa kọ́ ara yín, kí ẹ sì máa gba ara yín níyànjú* pẹ̀lú àwọn sáàmù,+ ìyìn sí Ọlọ́run, àwọn orin ẹ̀mí tí à ń fi ìmoore* kọ, kí ẹ máa kọrin sí Jèhófà* nínú ọkàn yín.+ 17 Ohunkóhun tí ẹ bá ń ṣe ní ọ̀rọ̀ tàbí ní ìṣe, ẹ máa ṣe ohun gbogbo ní orúkọ Jésù Olúwa, kí ẹ máa tipasẹ̀ rẹ̀ dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run tó jẹ́ Baba.+

18 Ẹ̀yin aya, ẹ máa tẹrí ba fún àwọn ọkọ yín,+ bó ṣe yẹ nínú Olúwa. 19 Ẹ̀yin ọkọ, ẹ máa nífẹ̀ẹ́ àwọn aya yín,+ ẹ má sì bínú sí wọn lọ́nà òdì.*+ 20 Ẹ̀yin ọmọ, ẹ máa gbọ́ràn sí àwọn òbí yín lẹ́nu nínú ohun gbogbo,+ nítorí èyí dára gidigidi lójú Olúwa. 21 Ẹ̀yin bàbá, ẹ má ṣe máa mú àwọn ọmọ yín bínú,*+ kí wọ́n má bàa sorí kodò.* 22 Ẹ̀yin ẹrú, ẹ máa gbọ́ràn sí àwọn ọ̀gá yín* lẹ́nu nínú ohun gbogbo,+ kì í ṣe nígbà tí wọ́n bá ń wò yín nìkan, torí kí ẹ lè tẹ́ èèyàn lọ́rùn,* àmọ́ ẹ máa fòótọ́ ọkàn ṣe é pẹ̀lú ìbẹ̀rù Jèhófà.* 23 Ohunkóhun tí ẹ bá ń ṣe, ẹ ṣe é tọkàntọkàn* bíi pé Jèhófà* lẹ̀ ń ṣe é fún,+ kì í ṣe èèyàn, 24 torí ẹ mọ̀ pé ọ̀dọ̀ Jèhófà* lẹ ti máa gba ogún náà bí èrè.+ Ẹ máa ṣẹrú fún Ọ̀gá náà, Kristi. 25 Ó dájú pé ẹni tó ń ṣe àìtọ́ á gba ẹ̀san ohun tó ṣe,+ kò sì sí ojúsàájú kankan.+

4 Ẹ̀yin ọ̀gá, ẹ máa fi òdodo àti ẹ̀tọ́ bá àwọn ẹrú yín lò, bí ẹ ṣe mọ̀ pé ẹ̀yin náà ní Ọ̀gá kan ní ọ̀run.+

2 Ẹ tẹra mọ́ àdúrà gbígbà,+ kí ẹ wà lójúfò nínú rẹ̀ pẹ̀lú ìdúpẹ́.+ 3 Lẹ́sẹ̀ kan náà, ẹ máa gbàdúrà fún wa+ pé kí Ọlọ́run ṣí ilẹ̀kùn fún ọ̀rọ̀ náà, kí a lè kéde àṣírí mímọ́ nípa Kristi, tí mo tìtorí rẹ̀ wà nínú ìdè ẹ̀wọ̀n,+ 4 kí n sì lè kéde rẹ̀ lọ́nà tó ṣe kedere bó ṣe yẹ kí n kéde rẹ̀.

5 Ẹ máa fi ọgbọ́n bá àwọn tó wà lóde lò, kí ẹ máa lo àkókò yín lọ́nà tó dára jù lọ.*+ 6 Ẹ jẹ́ kí ọ̀rọ̀ yín máa jẹ́ ọ̀rọ̀ onínúure, tí iyọ̀ dùn,+ kí ẹ lè mọ bó ṣe yẹ kí ẹ dá ẹnì kọ̀ọ̀kan lóhùn.+

7 Tíkíkù,+ arákùnrin mi ọ̀wọ́n tó jẹ́ òjíṣẹ́ olóòótọ́ àti ẹrú ẹlẹgbẹ́ mi nínú Olúwa, máa ròyìn gbogbo ohun tó ṣẹlẹ̀ sí mi fún yín. 8 Mò ń rán an sí yín kí ẹ lè mọ bí a ṣe ń ṣe sí, kí ó sì lè tu ọkàn yín lára. 9 Ó ń bọ̀ pẹ̀lú Ónísímù,+ arákùnrin mi olóòótọ́ àti olùfẹ́, ẹni tó ti àárín yín wá; wọ́n á sọ gbogbo ohun tó ń ṣẹlẹ̀ níbí fún yín.

10 Àrísítákọ́sì+ tí a jọ wà lẹ́wọ̀n kí yín, Máàkù+ mọ̀lẹ́bí Bánábà náà kí yín, (ẹni tí a sọ fún yín pé kí ẹ gbà tọwọ́tẹsẹ̀  + tó bá wá sọ́dọ̀ yín), 11 pẹ̀lú Jésù tí wọ́n ń pè ní Jọ́sítù, àwọn yìí jẹ́ ara àwọn tó dádọ̀dọ́.* Àwọn yìí nìkan la jọ ń ṣiṣẹ́ fún Ìjọba Ọlọ́run, wọ́n sì ti di orísun ìtùnú* fún mi gan-an. 12 Épáfírásì+ tó ti àárín yín wá, ẹrú Kristi Jésù, kí yín. Ìgbà gbogbo ló ń gbàdúrà lójú méjèèjì nítorí yín, pé níkẹyìn, kí ẹ lè dúró ní pípé, kí ẹ sì ní ìdánilójú nínú gbogbo ìfẹ́ Ọlọ́run. 13 Mo jẹ́rìí rẹ̀ pé ó ń sapá gan-an nítorí yín àti nítorí àwọn tó wà ní Laodíkíà àti ní Hirapólísì.

14 Lúùkù+ oníṣègùn tó jẹ́ olùfẹ́ kí yín, Démà+ náà kí yín. 15 Ẹ bá mi kí àwọn ará ní Laodíkíà, ẹ sì bá mi kí Nímífà àti ìjọ tó wà ní ilé rẹ̀.+ 16 Tí ẹ bá ti ka lẹ́tà yìí láàárín yín, ẹ ṣètò pé kí wọ́n kà á+ nínú ìjọ àwọn ará Laodíkíà, kí ẹ̀yin náà sì ka èyí tó wá láti Laodíkíà. 17 Bákan náà, ẹ sọ fún Ákípọ́sì+ pé: “Máa fiyè sí iṣẹ́ òjíṣẹ́ tí o gbà nínú Olúwa, kí o lè ṣe é láṣeyọrí.”

18 Ìkíni èmi Pọ́ọ̀lù nìyí, tí mo fi ọwọ́ ara mi kọ.+ Ẹ máa fi ìdè ẹ̀wọ̀n mi+ sọ́kàn. Kí inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí wà pẹ̀lú yín.

Ní Grk., “nínú ẹ̀mí.”

Wo Àfikún A5.

Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.

Tàbí “àsìkò.”

Ní Grk., “rí ojú mi nínú ẹran ara.”

Tàbí “gbé yín lọ bí ẹran tí a mú.”

Ìyẹn, ìwà àti ìṣe.

Tàbí “kọlà.”

Tàbí “ìkọlà.”

Tàbí “àìkọlà.”

Tàbí “wọ́gi lé ìwé àfọwọ́kọ.”

Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.

Tàbí kó jẹ́, “òun fúnra rẹ̀ ń.”

Ọ̀rọ̀ yìí wá látinú ẹ̀kọ́ àdììtú àwọn abọ̀rìṣà.

Lédè Gíríìkì, por·neiʹa. Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.

Tàbí “ṣe rìn.”

Tàbí “nígbà tí ẹ̀ ń gbé irú ìgbé ayé yẹn.”

Ní Grk., “ọkùnrin.”

Tàbí “ìkọlà.”

Tàbí “àìkọlà.”

“Sítíánì” ń tọ́ka sí àwọn tí kò lajú.

Tàbí “ìrẹ̀lẹ̀ ọkàn.”

Wo Àfikún A5.

Tàbí “máa darí ọkàn yín.”

Tàbí “bá ara yín wí.”

Tàbí “oore ọ̀fẹ́.”

Wo Àfikún A5.

Tàbí “ẹ má sì kanra mọ́ wọn.”

Tàbí “ni àwọn ọmọ yín lára.”

Tàbí “rẹ̀wẹ̀sì.”

Ní Grk., “ọ̀gá yín nípa tara.”

Ní Grk., “kì í ṣe àrójúṣe bíi ti àwọn tó máa ń fẹ́ wu èèyàn.”

Wo Àfikún A5.

Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀, “Ọkàn.”

Wo Àfikún A5.

Wo Àfikún A5.

Ní Grk., “máa ra àkókò pa dà.”

Tàbí “kọlà.”

Tàbí “àrànṣe afúnnilókun.”

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́