ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Sáàmù 104
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Sáàmù

      • Yin Ọlọ́run torí àwọn ohun àgbàyanu tó wà nínú ìṣẹ̀dá

        • Ayé máa wà títí láé (5)

        • Oúnjẹ àti wáìnì wà fún ẹni kíkú (15)

        • “Àwọn iṣẹ́ rẹ mà pọ̀ o!” (24)

        • ‘Tí a bá mú ẹ̀mí kúrò, wọ́n á kú’ (29)

Sáàmù 104:1

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ọkàn mi.”

  • *

    Tàbí “iyì.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Sm 103:1
  • +Sm 86:10
  • +1Kr 16:27; Isk 1:27, 28; Da 7:9

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    8/15/2008, ojú ìwé 13

Sáàmù 104:2

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jem 1:17; 1Jo 1:5
  • +Ais 40:22

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    8/15/2008, ojú ìwé 13

Sáàmù 104:3

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “sínú omi.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Sm 18:11; Emọ 9:6
  • +Di 33:26; Ais 19:1
  • +2Sa 22:11; Job 38:1

Sáàmù 104:4

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Isk 1:13; Heb 1:7, 14

Sáàmù 104:5

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “mú kí ó ta gbọ̀n-ọ́n gbọ̀n-ọ́n.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Job 38:4, 6; Sm 24:1, 2
  • +Onw 1:4

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Jí!,

    No. 5 2016 ojú ìwé 15

    Ilé Ìṣọ́,

    8/1/2008, ojú ìwé 31

Sáàmù 104:6

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 1:2

Sáàmù 104:7

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 1:9

Sáàmù 104:8

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Owe 8:25

Sáàmù 104:9

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Job 38:8-10; Sm 33:7; Owe 8:29; Jer 5:22

Sáàmù 104:11

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Jí!,

    3/8/1996, ojú ìwé 18

Sáàmù 104:13

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “Èso iṣẹ́.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Job 38:37; Sm 147:8; Jer 10:13; Emọ 9:6; Mt 5:45
  • +Sm 65:9; Iṣe 14:17

Sáàmù 104:14

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 1:29, 30; 9:3

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!, ẹ̀kọ́ 46

    Ilé Ìṣọ́,

    10/15/2011, ojú ìwé 8

Sáàmù 104:15

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Onw 9:7
  • +Onw 10:19

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!, ẹ̀kọ́ 43

    Ilé Ìṣọ́,

    10/15/2011, ojú ìwé 8

Sáàmù 104:17

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jer 8:7

Sáàmù 104:18

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Job 39:1
  • +Owe 30:26

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    3/15/2004, ojú ìwé 9

    7/15/1997, ojú ìwé 24

Sáàmù 104:19

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 1:16; Sm 19:6; Jer 31:35

Sáàmù 104:20

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 1:5; Sm 74:16; Ais 45:7

Sáàmù 104:21

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ọmọ kìnnìún tó tó ọdẹ ṣe (onígọ̀gọ̀).”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Emọ 3:4
  • +Sm 147:9

Sáàmù 104:24

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ne 9:6
  • +Owe 3:19; Jer 10:12

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Sún Mọ́ Jèhófà, ojú ìwé 55, 173-175

Sáàmù 104:25

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 1:21

Sáàmù 104:26

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Job 41:1

Sáàmù 104:27

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Sm 136:25; 145:15; 147:9; Mt 6:26

Sáàmù 104:28

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Lk 12:24
  • +Sm 107:9; 145:16

Sáàmù 104:29

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 3:19; Job 34:14, 15; Sm 146:3, 4; Onw 3:19, 20; 12:7

Sáàmù 104:30

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Job 33:4; Iṣe 17:28

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    5/15/2002, ojú ìwé 5

Sáàmù 104:31

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 1:31

Sáàmù 104:32

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 19:18

Sáàmù 104:33

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “kọrin.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Sm 13:6
  • +Sm 146:2

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!, ẹ̀kọ́ 14

Sáàmù 104:34

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí kó jẹ́, “Kí ohun tí mò ń rò nípa rẹ̀ dùn mọ́ni.”

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!, ẹ̀kọ́ 40

Sáàmù 104:35

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ọkàn mi.”

  • *

    Tàbí “Halelúyà!” “Jáà” ni ìkékúrú Jèhófà.

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Sm 37:10, 38; Owe 2:22

Àwọn míì

Sm 104:1Sm 103:1
Sm 104:1Sm 86:10
Sm 104:11Kr 16:27; Isk 1:27, 28; Da 7:9
Sm 104:2Jem 1:17; 1Jo 1:5
Sm 104:2Ais 40:22
Sm 104:3Sm 18:11; Emọ 9:6
Sm 104:3Di 33:26; Ais 19:1
Sm 104:32Sa 22:11; Job 38:1
Sm 104:4Isk 1:13; Heb 1:7, 14
Sm 104:5Job 38:4, 6; Sm 24:1, 2
Sm 104:5Onw 1:4
Sm 104:6Jẹ 1:2
Sm 104:7Jẹ 1:9
Sm 104:8Owe 8:25
Sm 104:9Job 38:8-10; Sm 33:7; Owe 8:29; Jer 5:22
Sm 104:13Job 38:37; Sm 147:8; Jer 10:13; Emọ 9:6; Mt 5:45
Sm 104:13Sm 65:9; Iṣe 14:17
Sm 104:14Jẹ 1:29, 30; 9:3
Sm 104:15Onw 9:7
Sm 104:15Onw 10:19
Sm 104:17Jer 8:7
Sm 104:18Job 39:1
Sm 104:18Owe 30:26
Sm 104:19Jẹ 1:16; Sm 19:6; Jer 31:35
Sm 104:20Jẹ 1:5; Sm 74:16; Ais 45:7
Sm 104:21Emọ 3:4
Sm 104:21Sm 147:9
Sm 104:24Ne 9:6
Sm 104:24Owe 3:19; Jer 10:12
Sm 104:25Jẹ 1:21
Sm 104:26Job 41:1
Sm 104:27Sm 136:25; 145:15; 147:9; Mt 6:26
Sm 104:28Lk 12:24
Sm 104:28Sm 107:9; 145:16
Sm 104:29Jẹ 3:19; Job 34:14, 15; Sm 146:3, 4; Onw 3:19, 20; 12:7
Sm 104:30Job 33:4; Iṣe 17:28
Sm 104:31Jẹ 1:31
Sm 104:32Ẹk 19:18
Sm 104:33Sm 13:6
Sm 104:33Sm 146:2
Sm 104:35Sm 37:10, 38; Owe 2:22
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
  • 1
  • 2
  • 3
  • 4
  • 5
  • 6
  • 7
  • 8
  • 9
  • 10
  • 11
  • 12
  • 13
  • 14
  • 15
  • 16
  • 17
  • 18
  • 19
  • 20
  • 21
  • 22
  • 23
  • 24
  • 25
  • 26
  • 27
  • 28
  • 29
  • 30
  • 31
  • 32
  • 33
  • 34
  • 35
Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
Sáàmù 104:1-35

Sáàmù

104 Jẹ́ kí n* yin Jèhófà.+

Ìwọ Jèhófà Ọlọ́run mi, o tóbi gan-an.+

O fi ògo* àti ọlá ńlá wọ ara rẹ láṣọ.+

 2 O fi ìmọ́lẹ̀+ bora bí aṣọ;

O na ọ̀run bí aṣọ àgọ́.+

 3 Ó tẹ́ igi àjà àwọn yàrá òkè rẹ̀ sínú omi lókè,*+

Ó fi àwọsánmà ṣe kẹ̀kẹ́ ẹṣin rẹ̀,+

Ó ń lọ lórí ìyẹ́ apá ẹ̀fúùfù.+

 4 Ó dá àwọn áńgẹ́lì rẹ̀ ní ẹ̀mí,

Ó dá àwọn òjíṣẹ́ rẹ̀ ní iná tó ń jó nǹkan run.+

 5 Ó ti gbé ayé kalẹ̀ sórí ìpìlẹ̀ rẹ̀;+

A kì yóò ṣí i nípò* títí láé àti láéláé.+

 6 O fi ibú omi bò ó bí aṣọ.+

Omi náà bo àwọn òkè.

 7 Bí wọ́n ṣe gbọ́ ìbáwí rẹ, wọ́n fẹsẹ̀ fẹ;+

Bí wọ́n ṣe gbọ́ ìró ààrá rẹ, ìbẹ̀rù mú kí wọ́n sá lọ

 8 —Àwọn òkè lọ sókè,+ àwọn àfonífojì sì lọ sílẹ̀—

Sí ibi tí o ṣe fún wọn.

 9 O pa ààlà tí wọn ò gbọ́dọ̀ kọjá,+

Kí wọ́n má bàa bo ayé mọ́.

10 Ó ń mú kí omi sun jáde ní àwọn àfonífojì;

Wọ́n ń ṣàn gba àárín àwọn òkè.

11 Wọ́n ń pèsè omi fún gbogbo ẹran inú igbó;

Àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ igbó ń fi wọ́n pa òùngbẹ.

12 Orí àwọn igi tó wà létí wọn ni àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run ń wọ̀ sí;

Wọ́n ń kọrin láàárín àwọn ẹ̀ka tó léwé dáadáa.

13 Ó ń bomi rin àwọn òkè láti àwọn yàrá òkè rẹ̀.+

Iṣẹ́ ọwọ́* rẹ ń tẹ́ ilẹ̀ ayé lọ́rùn.+

14 Ó ń mú kí koríko hù fún àwọn ẹran orí pápá láti jẹ

Àti ewéko fún ìlò aráyé,+

Kí oúnjẹ lè jáde látinú ilẹ̀

15 Àti wáìnì tó ń mú ọkàn èèyàn yọ̀,+

Òróró tó ń mú kí ojú dán

Àti oúnjẹ tó ń gbé ẹ̀mí ẹni kíkú ró.+

16 Àwọn igi Jèhófà rí omi mu,

Àwọn igi kédárì Lẹ́bánónì tó gbìn,

17 Ibẹ̀ ni àwọn ẹyẹ ń kọ́ ìtẹ́ sí.

Ilé ẹyẹ àkọ̀+ wà lórí àwọn igi júnípà.

18 Àwọn òkè gíga wà fún àwọn ewúrẹ́ orí òkè;+

Àwọn àpáta gàǹgà jẹ́ ibi ààbò fún àwọn gara orí àpáta.+

19 Ó dá òṣùpá láti máa sàmì àkókò;

Oòrùn mọ ìgbà tó yẹ kó wọ̀.+

20 O mú kí òkùnkùn ṣú, alẹ́ sì lẹ́,+

Gbogbo ẹranko inú igbó sì ń jẹ̀ kiri.

21 Àwọn ọmọ kìnnìún* ń ké ramúramù nítorí ẹran tí wọ́n fẹ́ pa jẹ,+

Wọ́n sì ń wá oúnjẹ wọn lọ́dọ̀ Ọlọ́run.+

22 Nígbà tí oòrùn bá yọ,

Wọ́n á pa dà, wọ́n á sì lọ dùbúlẹ̀ sínú ihò wọn.

23 Èèyàn á lọ sẹ́nu iṣẹ́ rẹ̀,

Á sì ṣiṣẹ́ títí di àṣálẹ́.

24 Àwọn iṣẹ́ rẹ mà pọ̀ o, Jèhófà!+

Gbogbo wọn lo fi ọgbọ́n ṣe.+

Ayé kún fún àwọn ohun tí o ṣe.

25 Ibẹ̀ ni òkun wà, ó tóbi, ó sì fẹ̀,

Àìmọye ohun alààyè ló wà nínú rẹ̀, èyí tó kéré àti èyí tó tóbi.+

26 Ibẹ̀ ni àwọn ọkọ̀ òkun ti ń rìn

Àti Léfíátánì,*+ tí o dá kí ó lè máa ṣeré nínú rẹ̀.

27 Gbogbo wọn ń dúró dè ọ́

Kí o lè fún wọn ní oúnjẹ lásìkò.+

28 Ohun tí o fún wọn ni wọ́n ń kó jọ.+

Tí o bá ṣí ọwọ́ rẹ, wọ́n á ní ọ̀pọ̀ ohun rere ní ànító.+

29 Tí o bá gbé ojú rẹ pa mọ́, ìdààmú á bá wọn.

Tí o bá mú ẹ̀mí wọn kúrò, wọ́n á kú, wọ́n á sì pa dà sí erùpẹ̀.+

30 Tí o bá rán ẹ̀mí rẹ jáde, a ó dá wọn,+

Ìwọ á sì sọ ojú ilẹ̀ di ọ̀tun.

31 Ògo Jèhófà yóò wà títí láé.

Jèhófà yóò máa yọ̀ lórí àwọn iṣẹ́ rẹ̀.+

32 Ó wo ayé, ayé sì mì tìtì;

Ó fọwọ́ kan àwọn òkè, wọ́n sì rú èéfín.+

33 Màá kọrin sí Jèhófà+ jálẹ̀ ayé mi;

Màá kọ orin ìyìn* sí Ọlọ́run mi ní gbogbo ìgbà tí mo bá fi wà láàyè.+

34 Kí èrò mi dùn mọ́ ọn.*

Èmi yóò máa yọ̀ nínú Jèhófà.

35 Àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ yóò pa rẹ́ kúrò láyé,

Àwọn ẹni burúkú kò sì ní sí mọ́.+

Jẹ́ kí n* yin Jèhófà. Ẹ yin Jáà!*

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́