ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Sáàmù 105
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Sáàmù

      • Àwọn iṣẹ́ òdodo Jèhófà lórí àwọn èèyàn rẹ̀

        • Ọlọ́run rántí májẹ̀mú rẹ̀ (8-10)

        • “Ẹ má fọwọ́ kan àwọn ẹni àmì òróró mi” (15)

        • Ọlọ́run lo Jósẹ́fù tí wọ́n mú lẹ́rú (17-22)

        • Àwọn iṣẹ́ ìyanu Ọlọ́run ní Íjíbítì (23-36)

        • Bí Ísírẹ́lì ṣe jáde kúrò ní Íjíbítì (37-39)

        • Ọlọ́run rántí ìlérí tó ṣe fún Ábúráhámù (42)

Sáàmù 105:1

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Sm 136:1
  • +1Kr 16:8-13; Sm 96:3; 145:11, 12; Ais 12:4

Sáàmù 105:2

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “kọ orin fún un.”

  • *

    Tàbí kó jẹ́, “sọ nípa.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Sm 77:12; 119:27

Sáàmù 105:3

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jer 9:24
  • +Sm 119:2

Sáàmù 105:4

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ibi tó wà.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Emọ 5:4; Sef 2:3

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    3/1/2000, ojú ìwé 15

Sáàmù 105:5

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Di 7:18, 19

Sáàmù 105:6

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “àtọmọdọ́mọ.” Ní Héb., “èso.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 3:6
  • +Ẹk 19:5, 6; Ais 41:8

Sáàmù 105:7

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 20:2; Sm 100:3
  • +1Kr 16:14-18; Ais 26:9; Ifi 15:4

Sáàmù 105:8

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “ọ̀rọ̀ tó pa láṣẹ.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ne 1:5
  • +Di 7:9; Lk 1:72, 73

Sáàmù 105:9

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 17:1, 2; 22:15-18
  • +Jẹ 26:3

Sáàmù 105:11

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 12:7; 13:14, 15; 15:18; 26:3; 28:13
  • +Sm 78:55

Sáàmù 105:12

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 34:30
  • +Jẹ 17:8; 23:4; 1Kr 16:19-22; Iṣe 7:4, 5

Sáàmù 105:13

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 20:1; 46:6

Sáàmù 105:14

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 31:7, 42
  • +Jẹ 12:17; 20:2, 3

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    3/15/2013, ojú ìwé 20-21

    4/15/2010, ojú ìwé 8

Sáàmù 105:15

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 26:9, 11

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    3/15/2013, ojú ìwé 20-21

    4/15/2010, ojú ìwé 8

    “Ete aiyeraiye,” ojú ìwé 94-95

Sáàmù 105:16

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “Ó ṣẹ́ gbogbo ọ̀pá búrẹ́dì.” Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ àwọn ọ̀pá tí wọ́n fi ń tọ́jú búrẹ́dì pa mọ́.

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 41:30, 54; 42:5; Iṣe 7:11

Sáàmù 105:17

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 37:28, 36; 45:4, 5; 50:20

Sáàmù 105:18

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “jẹ ẹsẹ̀ rẹ̀ níyà.”

  • *

    Tàbí “Ọkàn rẹ̀ wọnú irin.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 39:20

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    11/1/2014, ojú ìwé 14-15

Sáàmù 105:19

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Iṣe 7:10

Sáàmù 105:20

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 41:14

Sáàmù 105:21

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 41:39-41, 48; 45:8

Sáàmù 105:22

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “Kó lè de.”

  • *

    Tàbí “bó bá ṣe tẹ́ ọkàn rẹ̀ lọ́rùn.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 41:33, 38

Sáàmù 105:23

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 46:4, 6

Sáàmù 105:24

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 1:7; Iṣe 7:17
  • +Ẹk 1:8, 9

Sáàmù 105:25

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 1:10; Iṣe 7:18, 19

Sáàmù 105:26

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 3:10; 4:12; 6:11
  • +Ẹk 4:14; 7:1

Sáàmù 105:27

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ne 9:10; Sm 78:43-51

Sáàmù 105:28

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 10:22, 23

Sáàmù 105:29

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 7:20, 21

Sáàmù 105:30

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 8:6

Sáàmù 105:31

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 8:17, 24

Sáàmù 105:32

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ọwọ́ iná.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 9:23-26

Sáàmù 105:34

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 10:13-15

Sáàmù 105:36

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 12:29

Sáàmù 105:37

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 15:13, 14; Ẹk 3:22; 12:35, 36

Sáàmù 105:38

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “wọn.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 12:33

Sáàmù 105:39

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ìkùukùu.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 14:19, 20
  • +Ẹk 13:21

Sáàmù 105:40

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Sm 78:27
  • +Ẹk 16:12-15; Sm 78:24

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    6/1/2014, ojú ìwé 8

Sáàmù 105:41

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 17:6; 1Kọ 10:1, 4
  • +Sm 78:15, 16

Sáàmù 105:42

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 12:7; 15:13, 14; Ẹk 2:24; Di 9:5

Sáàmù 105:43

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Nọ 33:3

Sáàmù 105:44

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Joṣ 11:23; 21:43; Ne 9:22; Sm 78:55; Iṣe 13:19
  • +Di 6:10, 11; Joṣ 5:11, 12

Sáàmù 105:45

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “Halelúyà!” “Jáà” ni ìkékúrú Jèhófà.

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Di 4:40

Àwọn míì

Sm 105:1Sm 136:1
Sm 105:11Kr 16:8-13; Sm 96:3; 145:11, 12; Ais 12:4
Sm 105:2Sm 77:12; 119:27
Sm 105:3Jer 9:24
Sm 105:3Sm 119:2
Sm 105:4Emọ 5:4; Sef 2:3
Sm 105:5Di 7:18, 19
Sm 105:6Ẹk 3:6
Sm 105:6Ẹk 19:5, 6; Ais 41:8
Sm 105:7Ẹk 20:2; Sm 100:3
Sm 105:71Kr 16:14-18; Ais 26:9; Ifi 15:4
Sm 105:8Ne 1:5
Sm 105:8Di 7:9; Lk 1:72, 73
Sm 105:9Jẹ 17:1, 2; 22:15-18
Sm 105:9Jẹ 26:3
Sm 105:11Jẹ 12:7; 13:14, 15; 15:18; 26:3; 28:13
Sm 105:11Sm 78:55
Sm 105:12Jẹ 34:30
Sm 105:12Jẹ 17:8; 23:4; 1Kr 16:19-22; Iṣe 7:4, 5
Sm 105:13Jẹ 20:1; 46:6
Sm 105:14Jẹ 31:7, 42
Sm 105:14Jẹ 12:17; 20:2, 3
Sm 105:15Jẹ 26:9, 11
Sm 105:16Jẹ 41:30, 54; 42:5; Iṣe 7:11
Sm 105:17Jẹ 37:28, 36; 45:4, 5; 50:20
Sm 105:18Jẹ 39:20
Sm 105:19Iṣe 7:10
Sm 105:20Jẹ 41:14
Sm 105:21Jẹ 41:39-41, 48; 45:8
Sm 105:22Jẹ 41:33, 38
Sm 105:23Jẹ 46:4, 6
Sm 105:24Ẹk 1:7; Iṣe 7:17
Sm 105:24Ẹk 1:8, 9
Sm 105:25Ẹk 1:10; Iṣe 7:18, 19
Sm 105:26Ẹk 3:10; 4:12; 6:11
Sm 105:26Ẹk 4:14; 7:1
Sm 105:27Ne 9:10; Sm 78:43-51
Sm 105:28Ẹk 10:22, 23
Sm 105:29Ẹk 7:20, 21
Sm 105:30Ẹk 8:6
Sm 105:31Ẹk 8:17, 24
Sm 105:32Ẹk 9:23-26
Sm 105:34Ẹk 10:13-15
Sm 105:36Ẹk 12:29
Sm 105:37Jẹ 15:13, 14; Ẹk 3:22; 12:35, 36
Sm 105:38Ẹk 12:33
Sm 105:39Ẹk 14:19, 20
Sm 105:39Ẹk 13:21
Sm 105:40Sm 78:27
Sm 105:40Ẹk 16:12-15; Sm 78:24
Sm 105:41Ẹk 17:6; 1Kọ 10:1, 4
Sm 105:41Sm 78:15, 16
Sm 105:42Jẹ 12:7; 15:13, 14; Ẹk 2:24; Di 9:5
Sm 105:43Nọ 33:3
Sm 105:44Joṣ 11:23; 21:43; Ne 9:22; Sm 78:55; Iṣe 13:19
Sm 105:44Di 6:10, 11; Joṣ 5:11, 12
Sm 105:45Di 4:40
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
  • 1
  • 2
  • 3
  • 4
  • 5
  • 6
  • 7
  • 8
  • 9
  • 10
  • 11
  • 12
  • 13
  • 14
  • 15
  • 16
  • 17
  • 18
  • 19
  • 20
  • 21
  • 22
  • 23
  • 24
  • 25
  • 26
  • 27
  • 28
  • 29
  • 30
  • 31
  • 32
  • 33
  • 34
  • 35
  • 36
  • 37
  • 38
  • 39
  • 40
  • 41
  • 42
  • 43
  • 44
  • 45
Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
Sáàmù 105:1-45

Sáàmù

105 Ẹ fi ọpẹ́ fún Jèhófà,+ ẹ ké pe orúkọ rẹ̀,

Ẹ jẹ́ kí àwọn èèyàn mọ àwọn ohun tí ó ṣe!+

 2 Ẹ kọrin sí i, ẹ fi orin yìn ín,*

Ẹ máa ronú lórí* gbogbo àwọn iṣẹ́ àgbàyanu rẹ̀.+

 3 Ẹ máa fi orúkọ mímọ́ rẹ̀ yangàn.+

Kí ọkàn àwọn tó ń wá Jèhófà máa yọ̀.+

 4 Ẹ máa wá Jèhófà+ àti agbára rẹ̀.

Ẹ máa wá ojú rẹ̀* nígbà gbogbo.

 5 Ẹ máa rántí àwọn iṣẹ́ àgbàyanu tó ti ṣe,

Àwọn iṣẹ́ ìyanu rẹ̀ àti àwọn ìdájọ́ tó kéde,+

 6 Ẹ̀yin ọmọ* Ábúráhámù ìránṣẹ́ rẹ̀,+

Ẹ̀yin ọmọ Jékọ́bù, ẹ̀yin àyànfẹ́ rẹ̀.+

 7 Òun ni Jèhófà Ọlọ́run wa.+

Àwọn ìdájọ́ rẹ̀ kárí ayé.+

 8 Ó ń rántí májẹ̀mú rẹ̀ títí láé,+

Ìlérí tó ṣe* títí dé ẹgbẹ̀rún ìran,+

 9 Májẹ̀mú tó bá Ábúráhámù dá+

Àti ìbúra rẹ̀ fún Ísákì,+

10 Èyí tó gbé kalẹ̀ bí ìlànà fún Jékọ́bù

Àti bíi májẹ̀mú tó wà títí láé fún Ísírẹ́lì,

11 Ó ní, “Màá fún ọ ní ilẹ̀ Kénáánì+

Bí ogún tí a pín fún yín.”+

12 Èyí jẹ́ nígbà tí wọ́n kéré níye,+

Bẹ́ẹ̀ ni, tí wọ́n kéré níye gan-an, tí wọ́n sì jẹ́ àjèjì ní ilẹ̀ náà.+

13 Wọ́n ń rìn kiri láti orílẹ̀-èdè dé orílẹ̀-èdè,

Láti ọ̀dọ̀ ìjọba kan dé ọ̀dọ̀ àwọn èèyàn míì.+

14 Kò gbà kí ẹnikẹ́ni ni wọ́n lára,+

Ṣùgbọ́n nítorí wọn, ó bá àwọn ọba wí,+

15 Ó ní, “Ẹ má fọwọ́ kan àwọn ẹni àmì òróró mi,

Ẹ má sì ṣe ohun búburú sí àwọn wòlíì mi.”+

16 Ó pe ìyàn wá sórí ilẹ̀ náà;+

Ó dí ibi tí búrẹ́dì ń gbà wọlé sọ́dọ̀ wọn.*

17 Ó rán ọkùnrin kan lọ ṣáájú wọn,

Jósẹ́fù, ẹni tí wọ́n tà lẹ́rú.+

18 Wọ́n fi ṣẹkẹ́ṣẹkẹ̀ de ẹsẹ̀ rẹ̀,*+

Wọ́n fi irin de ọrùn rẹ̀;*

19 Títí ọ̀rọ̀ rẹ̀ fi ṣẹ,+

Ọ̀rọ̀ Jèhófà ló yọ́ ọ mọ́.

20 Ọba ní kí wọ́n lọ tú u sílẹ̀,+

Alákòóso àwọn èèyàn náà dá a sílẹ̀.

21 Ó fi í ṣe ọ̀gá lórí agbo ilé rẹ̀

Àti alákòóso lórí gbogbo ohun ìní rẹ̀,+

 22 Kó lè lo àṣẹ lórí* àwọn ìjòyè rẹ̀ bó ṣe fẹ́,*

Kó sì kọ́ àwọn àgbààgbà rẹ̀ ní ọgbọ́n.+

23 Lẹ́yìn náà, Ísírẹ́lì wá sí Íjíbítì,+

Jékọ́bù sì di àjèjì ní ilẹ̀ Hámù.

24 Ọlọ́run mú kí àwọn èèyàn rẹ̀ pọ̀ rẹpẹtẹ;+

Ó mú kí wọ́n lágbára ju àwọn ọ̀tá wọn lọ,+

 25 Àwọn tó jẹ́ kí ọkàn wọn yí pa dà kí wọ́n lè kórìíra àwọn èèyàn rẹ̀,

Kí wọ́n sì dìtẹ̀ mọ́ àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀.+

26 Ó rán Mósè ìránṣẹ́ rẹ̀+

Àti Áárónì,+ ẹni tí ó yàn.

27 Wọ́n ṣe àwọn iṣẹ́ àmì rẹ̀ láàárín wọn,

Àwọn iṣẹ́ ìyanu rẹ̀ ní ilẹ̀ Hámù.+

28 Ó rán òkùnkùn, ilẹ̀ náà sì ṣókùnkùn;+

Wọn kò ṣọ̀tẹ̀ sí ọ̀rọ̀ rẹ̀.

29 Ó sọ omi wọn di ẹ̀jẹ̀,

Ó sì pa ẹja wọn.+

30 Àwọn àkèré ń gbá yìn-ìn ní ilẹ̀ wọn,+

Kódà nínú àwọn yàrá ọba.

31 Ó pàṣẹ pé kí àwọn eṣinṣin mùjẹ̀mùjẹ̀ ya wọlé,

Kí kòkòrò abìyẹ́ tó ń mùjẹ̀ sì bo gbogbo ilẹ̀ wọn.+

32 Ó sọ òjò wọn di yìnyín,

Ó sì rán mànàmáná* sí ilẹ̀ wọn.+

33 Ó kọ lu àjàrà wọn àti igi ọ̀pọ̀tọ́ wọn,

Ó sì ṣẹ́ àwọn igi tó wà ní ilẹ̀ wọn sí wẹ́wẹ́.

34 Ó ní kí àwọn eéṣú ya wọlé,

Àwọn ọmọ eéṣú tí kò níye.+

35 Wọ́n jẹ gbogbo ewéko ilẹ̀ náà,

Wọ́n sì jẹ irè oko wọn.

36 Lẹ́yìn náà, ó pa gbogbo àkọ́bí tó wà ní ilẹ̀ wọn,+

Ìbẹ̀rẹ̀ agbára ìbímọ wọn.

37 Ó mú àwọn èèyàn rẹ̀ jáde tàwọn ti fàdákà àti wúrà;+

Ìkankan lára àwọn ẹ̀yà rẹ̀ kò sì kọsẹ̀.

38 Íjíbítì yọ̀ nígbà tí wọ́n kúrò,

Nítorí ìbẹ̀rù Ísírẹ́lì* ti bò wọ́n.+

39 Ó na àwọsánmà* bo àwọn èèyàn rẹ̀,+

Ó sì pèsè iná láti fún wọn ní ìmọ́lẹ̀ ní òru.+

40 Wọ́n béèrè ẹran, ó sì fún wọn ní àparò;+

Ó ń fi oúnjẹ láti ọ̀run tẹ́ wọn lọ́rùn.+

41 Ó ṣí àpáta, omi sì ṣàn jáde;+

Ó ṣàn gba aṣálẹ̀ kọjá bí odò.+

42 Nítorí ó rántí ìlérí mímọ́ tó ṣe fún Ábúráhámù ìránṣẹ́ rẹ̀.+

43 Torí náà, ó mú àwọn èèyàn rẹ̀ jáde tayọ̀tayọ̀,+

Ó mú àwọn àyànfẹ́ rẹ̀ jáde pẹ̀lú igbe ìdùnnú.

44 Ó fún wọn ní ilẹ̀ àwọn orílẹ̀-èdè;+

Wọ́n jogún ohun tí àwọn míì ti ṣiṣẹ́ kára láti mú jáde,+

45 Kí wọ́n lè máa pa àwọn àṣẹ rẹ̀ mọ́,+

Kí wọ́n sì máa tẹ̀ lé àwọn òfin rẹ̀.

Ẹ yin Jáà!*

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́