ORIN SÓLÓMỌ́NÌ
1 Orin tó ju orin lọ,* tí Sólómọ́nì+ kọ:
3 Bí àwọn òróró rẹ ṣe ń ta sánsán ń tuni lára.+
Orúkọ rẹ dà bí òróró tó ń ta sánsán tí wọ́n tú jáde.+
Ìdí nìyẹn tí àwọn ọ̀dọ́bìnrin fi nífẹ̀ẹ́ rẹ.
4 Mú mi dání;* jẹ́ ká sáré.
Ọba ti mú mi wọnú àwọn yàrá rẹ̀ tó wà ní inú!
Jẹ́ kí inú wa máa dùn, ká sì jọ máa yọ̀.
Jẹ́ ká yin* ọ̀rọ̀ ìfẹ́ tí ò ń fi hàn sí mi ju ọ̀rọ̀ wáìnì lọ.
Abájọ tí wọ́n* fi nífẹ̀ẹ́ rẹ.
5 Ẹ̀yin ọmọbìnrin Jerúsálẹ́mù, mo dúdú lóòótọ́, àmọ́ òrékelẹ́wà ni mí,
Bí àwọn àgọ́ tí wọ́n fi Kídárì ṣe,+ bí àwọn aṣọ àgọ́+ Sólómọ́nì.
6 Ẹ má tẹjú mọ́ mi torí pé mo dúdú,
Oòrùn ló sọ mí dà bẹ́ẹ̀.
Àwọn ọmọ ìyá mi bínú sí mi;
Wọ́n ní kí n máa bójú tó àwọn ọgbà àjàrà,
Àmọ́ mi ò bójú tó ọgbà àjàrà tèmi.
7 Ìwọ ẹni tí mo nífẹ̀ẹ́* gan-an, sọ fún mi,
Ibi ìjẹko tí o ti ń da àwọn ẹran rẹ,+
Ibi tí ò ń mú kí wọ́n dùbúlẹ̀ sí ní ọ̀sán.
Ṣé ó wá yẹ kí n dà bí obìnrin tó fi aṣọ bojú*
Nínú agbo ẹran àwọn ọ̀rẹ́ rẹ?”
8 “Tó ò bá mọ̀, ìwọ obìnrin tó rẹwà jù,
Gba ibi tí agbo ẹran náà gbà,
Kí o sì jẹ́ kí àwọn ọmọ ewúrẹ́ rẹ máa jẹko lẹ́gbẹ̀ẹ́ àgọ́ àwọn olùṣọ́ àgùntàn.”
9 “Olólùfẹ́ mi, mo fi ọ́ wé abo ẹṣin* láàárín àwọn kẹ̀kẹ́ ẹṣin Fáráò.+
10 Ohun ọ̀ṣọ́* mú kí ẹ̀rẹ̀kẹ́ rẹ lẹ́wà,
Ìlẹ̀kẹ̀ ọrùn rẹ sì mú kí ọrùn rẹ lẹ́wà.
11 A máa fi wúrà ṣe ohun ọ̀ṣọ́* fún ọ,
A ó sì fi fàdákà sí i lára.”
13 Lójú mi, olólùfẹ́ mi dà bí àpò òjíá+ tó ń ta sánsán,
Tó ń sùn mọ́jú láàárín ọmú mi.
15 “Wò ó! O rẹwà gan-an, olólùfẹ́ mi.
Wò ó! O rẹwà gan-an. Ojú rẹ rí bíi ti àdàbà.”+
16 “Wò ó! O rẹwà púpọ̀,* olólùfẹ́ mi, o sì wù mí gan-an.+
Àárín ewéko ni ibùsùn wa.
17 Igi kédárì ni àwọn òpó ilé* wa,
Igi júnípà ni a sì fi ró ilé wa.
2 “Bí òdòdó lílì láàárín àwọn ẹ̀gún,
Ni olólùfẹ́ mi rí láàárín àwọn ọmọbìnrin.”
3 “Bí igi ápù láàárín àwọn igi inú igbó,
Ni olólùfẹ́ mi rí láàárín àwọn ọmọkùnrin.
Ó wù mí tọkàntọkàn pé kí n jókòó sábẹ́ ibòji rẹ̀,
Èso rẹ̀ sì ń dùn mọ́ mi lẹ́nu.
4 Ó mú mi wá sínú ilé àsè,*
Ó sì fi ìfẹ́ rẹ̀ bò mí.
5 Ẹ fún mi ní ìṣù àjàrà gbígbẹ+ kí ara lè tù mí;
Ẹ fún mi ní èso ápù kí n lè lókun,
Torí òjòjò ìfẹ́ ń ṣe mí.
7 Mo mú kí ẹ búra, ẹ̀yin ọmọbìnrin Jerúsálẹ́mù,
Kí ẹ fi àwọn egbin+ àti àwọn abo àgbọ̀nrín inú pápá búra:
Pé kí ẹ má ṣe ta ìfẹ́ jí, ẹ má sì ru ìfẹ́ sókè nínú mi, títí á fi wá fúnra rẹ̀.+
8 Mo gbọ́ ìró olólùfẹ́ mi!
Wò ó! Òun ló ń bọ̀ yìí,
Ó ń gun àwọn òkè ńlá, ó ń tọ pọ́n-ún pọ́n-ún lórí àwọn òkè kéékèèké.
9 Olólùfẹ́ mi dà bí egbin, bí akọ ọmọ àgbọ̀nrín.+
Òun nìyẹn, ó dúró sí ẹ̀yìn ògiri wa,
Ó ń yọjú lójú fèrèsé,*
Ó ń yọjú níbi àwọn fèrèsé tó ní asẹ́ onígi.
10 Olólùfẹ́ mi bá mi sọ̀rọ̀, ó sọ fún mi pé:
‘Dìde, ìfẹ́ mi,
Arẹwà mi, tẹ̀ lé mi ká lọ.
11 Wò ó! Ìgbà òtútù* ti kọjá.
Òjò ò rọ̀ mọ́, ó ti dáwọ́ dúró.
12 Òdòdó ti yọ ní ilẹ̀ wa,+
Àkókò ti tó láti rẹ́wọ́ ọ̀gbìn,+
A sì gbọ́ orin tí ẹyẹ oriri ń kọ ní ilẹ̀ wa.+
13 Àwọn èso tó kọ́kọ́ yọ lórí igi ọ̀pọ̀tọ́ ti pọ́n;+
Àwọn àjàrà ti yọ òdòdó, wọ́n sì ń ta sánsán.
Dìde, olólùfẹ́ mi, máa bọ̀.
Arẹwà mi, tẹ̀ lé mi ká lọ.
14 Ìwọ àdàbà mi, tí o wà nínú ihò àpáta,+
Níbi kọ́lọ́fín òkè tó dà gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́,
Jẹ́ kí n rí ọ, kí n sì gbọ́ ohùn rẹ,+
Torí ohùn rẹ dùn, ìrísí rẹ sì dára gan-an.’”+
15 “Bá wa mú àwọn kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀,
Àwọn kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ kéékèèké tó ń ba àwọn ọgbà àjàrà jẹ́,
Torí àwọn ọgbà àjàrà wa ti yọ òdòdó.”
16 “Èmi ni mo ni olólùfẹ́ mi, òun ló sì ni mí.+
Ó ń tọ́jú àwọn àgùntàn+ láàárín àwọn òdòdó lílì.+
17 Títí afẹ́fẹ́ yóò fi bẹ̀rẹ̀ sí í fẹ́,* tí òjìji kò sì ní sí mọ́,
Tètè pa dà, ìwọ olólùfẹ́ mi,
Bí egbin+ tàbí akọ ọmọ àgbọ̀nrín+ lórí àwọn òkè tó yà wá sọ́tọ̀.*
Mo wá a, àmọ́ mi ò rí i.+
2 Màá dìde, màá sì lọ káàkiri inú ìlú;
Kí n lè wá ẹni tí mo nífẹ̀ẹ́,*
Ní ojú ọ̀nà àti ní àwọn ojúde ìlú.
Mo wá a, àmọ́ mi ò rí i.
3 Àwọn tó ń ṣọ́ ìlú rí mi nígbà tí wọ́n ń lọ yí ká.+
Mo bi wọ́n pé, ‘Ṣé ẹ bá mi rí olólùfẹ́ mi?’*
4 Bí mo ṣe ní kí n kúrò lọ́dọ̀ wọn báyìí
Ni mo rí olólùfẹ́ mi.*
5 Mo mú kí ẹ búra, ẹ̀yin ọmọbìnrin Jerúsálẹ́mù,
Kí ẹ fi àwọn egbin àti àwọn abo àgbọ̀nrín inú pápá búra:
Pé kí ẹ má ṣe ta ìfẹ́ jí, ẹ má sì ru ìfẹ́ sókè nínú mi, títí á fi wá fúnra rẹ̀.”+
6 “Kí ló ń jáde látinú aginjù yìí, tó ń rú túú bí èéfín,
Tí òjíá àti tùràrí ń ta sánsán lára rẹ̀,
Pẹ̀lú gbogbo àtíkè oníṣòwò tó ń ta sánsán?”+
7 “Wò ó! Ìtẹ́ Sólómọ́nì ni.
Ọgọ́ta (60) alágbára ọkùnrin ló yí i ká,
Lára àwọn alágbára ọkùnrin ní Ísírẹ́lì,+
8 Gbogbo wọn ló ní idà,
Gbogbo wọn kọ́ṣẹ́ ogun jíjà,
Kálukú fi idà rẹ̀ sẹ́gbẹ̀ẹ́
Torí ewu ní òru.”
10 Fàdákà ló fi ṣe àwọn òpó rẹ̀,
Wúrà ló fi gbé e ró.
Òwú aláwọ̀ pọ́pù ló fi ṣe ìjókòó rẹ̀;
Àwọn ọmọbìnrin Jerúsálẹ́mù
Ṣe inú rẹ̀ lọ́ṣọ̀ọ́ tìfẹ́tìfẹ́.”
11 “Ẹ jáde lọ, ẹ̀yin ọmọbìnrin Síónì,
Kí ẹ lọ wo Ọba Sólómọ́nì
Tó dé adé ọkọ ìyàwó* tí ìyá rẹ̀+ ṣe fún un
Ní ọjọ́ ìgbéyàwó rẹ̀,
Ní ọjọ́ tí inú rẹ̀ ń dùn.”
4 “Wò ó! O rẹwà gan-an, olólùfẹ́ mi.
Wò ó! O rẹwà gan-an.
Ojú rẹ rí bíi ti àdàbà, lábẹ́ aṣọ tí o fi bojú.
Irun rẹ dà bí agbo ewúrẹ́
Tí wọ́n ń rọ́ bọ̀ láti orí àwọn òkè Gílíádì.+
2 Eyín rẹ dà bí agbo àgùntàn tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ gé irun wọn,
Tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ wẹ̀ fún,
Gbogbo wọn bí ìbejì,
Ọmọ ìkankan nínú wọn ò sì sọ nù.
3 Ètè rẹ rí bí òwú aláwọ̀ rírẹ̀dòdò,
Ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ sì dùn.
Ẹ̀rẹ̀kẹ́* rẹ rí bí awẹ́ pómégíránétì
Lábẹ́ aṣọ tí o fi bojú.
5 Ọmú rẹ méjèèjì dà bí ọmọ àgbọ̀nrín méjì,
Ó dà bí ọmọ egbin+ tí wọ́n jẹ́ ìbejì,
Tí wọ́n ń jẹko láàárín àwọn òdòdó lílì.”
6 “Màá lọ sórí òkè òjíá,
Màá gba ọ̀nà òkè tùràrí lọ,+
Títí afẹ́fẹ́ yóò fi bẹ̀rẹ̀ sí í fẹ́,* tí òjìji kò sì ní sí mọ́.”
8 Jẹ́ ká jọ máa bọ̀ láti Lẹ́bánónì, ìyàwó mi,
Jẹ́ ká jọ máa bọ̀ láti Lẹ́bánónì.+
Sọ̀ kalẹ̀ láti téńté òkè Ámánà,*
Láti téńté òkè Sénírì, téńté òkè Hámónì,+
Látinú ihò kìnnìún, látorí àwọn òkè tí àwọn àmọ̀tẹ́kùn ń gbé.
9 O ti gbà mí lọ́kàn,+ arábìnrin mi, ìyàwó mi,
Bí o ṣe ṣíjú wò mí báyìí, tí mo rí ọ̀kan nínú ẹ̀gbà ọrùn rẹ,
Bẹ́ẹ̀ lo gbà mí lọ́kàn.
10 Arábìnrin mi, ìyàwó mi, ìfẹ́ tí ò ń fi hàn sí mi mà dára o!+
11 Oyin inú afárá+ ń kán tótó ní ètè rẹ, ìyàwó mi.
Oyin àti wàrà wà lábẹ́ ahọ́n rẹ,+
Aṣọ rẹ sì ń ta sánsán bíi ti Lẹ́bánónì.
12 Arábìnrin mi, ìyàwó mi, dà bí ọgbà tí wọ́n tì,
Ọgbà tí wọ́n tì, orísun omi tí wọ́n sé pa.
13 Àwọn ẹ̀ka* rẹ dà bí ọgbà pómégíránétì,*
Tó ní àwọn èso tó dára jù, àwọn ewé làálì pẹ̀lú ewé sípíkénádì,
14 Sípíkénádì+ àti òdòdó sáfúrónì, pòròpórò*+ àti igi sínámónì,+
Pẹ̀lú oríṣiríṣi igi tùràrí, òjíá àti álóè+
Àti gbogbo lọ́fínńdà tó dára jù.+
15 Orísun omi inú ọgbà ni ọ́, kànga omi tó mọ́
Àti odò tó ń ṣàn láti Lẹ́bánónì.+
16 Jí, ìwọ atẹ́gùn àríwá;
Wọlé wá, ìwọ atẹ́gùn gúúsù.
Fẹ́* sórí ọgbà mi.
Jẹ́ kí ìtasánsán rẹ̀ gbalẹ̀ kan.”
“Jẹ́ kí olólùfẹ́ mi wá sínú ọgbà rẹ̀
Kó sì jẹ àwọn èso rẹ̀ tó dára jù lọ.”
5 “Mo ti wọnú ọgbà mi,+
Ìwọ arábìnrin mi, ìyàwó mi.
Mo ti já òjíá mi àti ewéko olóòórùn dídùn mi.+
Mo ti jẹ afárá oyin mi àti oyin mi;
Mo ti mu wáìnì mi àti wàrà mi.”+
“Ẹ jẹun, ẹ̀yin ọ̀rẹ́ ọ̀wọ́n!
Ẹ mu ìfẹ́,+ kí ẹ sì yó!”
2 “Mo ti sùn lọ, àmọ́ ọkàn mi ò sùn.+
Mo gbọ́ ìró olólùfẹ́ mi tó ń kan ilẹ̀kùn!”
‘Ṣílẹ̀kùn fún mi, arábìnrin mi, olólùfẹ́ mi,
Àdàbà mi, ẹni tí ẹwà rẹ̀ ò lábùlà!
Torí ìrì ti sẹ̀ sí mi lórí,
Ìrì òru+ ti mú kí irun mi tutù.’
3 Mo ti bọ́ aṣọ mi.
Ṣé kí n tún wọ̀ ọ́ pa dà ni?
Mo ti fọ ẹsẹ̀ mi.
Ṣé kí n tún jẹ́ kó dọ̀tí ni?
4 Olólùfẹ́ mi mú ọwọ́ kúrò lára ihò ilẹ̀kùn,
Ọkàn mi sì túbọ̀ fà sí i.
5 Mo dìde kí n lè ṣílẹ̀kùn fún olólùfẹ́ mi;
Òjíá ń kán tótó ní ọwọ́ mi,
Òjíá olómi ń kán ní àwọn ìka mi,
Sára ọwọ́ ilẹ̀kùn.
6 Mo ṣílẹ̀kùn fún olólùfẹ́ mi,
Àmọ́ olólùfẹ́ mi ti pa dà, ó ti lọ.
Àfi bíi pé kò sí ìrètí fún mi* nígbà tó lọ.*
Mo wá a, ṣùgbọ́n mi ò rí i.+
Mo pè é, àmọ́ kò dá mi lóhùn.
7 Àwọn tó ń ṣọ́ ìlú rí mi nígbà tí wọ́n ń lọ yí ká.
Wọ́n lù mí, wọ́n ṣe mí léṣe.
Àwọn tó ń ṣọ́ ògiri ṣí ìborùn* mi kúrò lára mi.
8 Mo mú kí ẹ búra, ẹ̀yin ọmọbìnrin Jerúsálẹ́mù:
Tí ẹ bá rí olólùfẹ́ mi,
Kí ẹ sọ fún un pé òjòjò ìfẹ́ ń ṣe mí.”
9 “Kí ló mú kí olólùfẹ́ rẹ dára ju àwọn olólùfẹ́ míì lọ,
Ìwọ tó rẹwà jù nínú àwọn obìnrin?
Kí ló mú kí olólùfẹ́ rẹ dára ju àwọn olólùfẹ́ míì lọ,
Tí o fi mú ká ṣe irú ìbúra yìí?”
10 “Olólùfẹ́ mi rẹwà, ó sì mọ́ra;
Kò sí ẹni tí a lè fi í wé láàárín ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá ọkùnrin.
11 Wúrà ni orí rẹ̀, wúrà tó dára jù.
Irun orí rẹ̀ dà bí imọ̀ ọ̀pẹ tó ń fẹ́ lẹ́lẹ́,*
Ó dúdú bí ẹyẹ ìwò.
12 Ojú rẹ̀ dà bí àwọn àdàbà tó wà létí odò,
Tí wọ́n ń wẹ̀ nínú wàrà,
Tí wọ́n wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ omi tó kún.*
13 Ẹ̀rẹ̀kẹ́ rẹ̀ dà bí ebè tí wọ́n gbin ewé tó ń ta sánsán sí,+
Òkìtì ewéko tó ń ta sánsán.
Ètè rẹ̀ dà bí òdòdó lílì, òjíá olómi+ sì ń kán tótó ní ètè rẹ̀.
14 Ọwọ́ rẹ̀ dà bí òpó wúrà, tí wọ́n fi kírísóláítì ṣe lọ́ṣọ̀ọ́.
Ikùn rẹ̀ dà bí eyín erin tó ń dán, tí wọ́n fi òkúta sàfáyà bò.
15 Ẹsẹ̀ rẹ̀ dà bí àwọn òpó tí wọ́n fi òkúta mábù ṣe, tó ní ìtẹ́lẹ̀ wúrà tó dára jù.
Ó rí bíi Lẹ́bánónì, kò sí ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ bí àwọn igi kédárì.+
Ẹ̀yin ọmọbìnrin Jerúsálẹ́mù, olólùfẹ́ mi nìyí, òun lẹni tí mo nífẹ̀ẹ́.”
6 “Ibo ni olólùfẹ́ rẹ lọ,
Ìwọ tó rẹwà jù nínú àwọn obìnrin?
Ibo ni olólùfẹ́ rẹ gbà?
Jẹ́ ká jọ wá a lọ.”
2 “Olólùfẹ́ mi ti lọ sí ọgbà rẹ̀,
Síbi ebè tí wọ́n gbin àwọn ewé tó ń ta sánsán sí,
Kó lè tọ́jú àwọn àgùntàn nínú ọgbà,
Kó sì já àwọn òdòdó lílì.+
3 Olólùfẹ́ mi ló ni mí,
Èmi ni mo sì ni olólùfẹ́ mi.+
Ó ń tọ́jú àwọn àgùntàn láàárín àwọn òdòdó lílì.”+
4 “Olólùfẹ́ mi,+ o rẹwà bíi Tírísà,*+
O wuni bíi Jerúsálẹ́mù,+
O gbayì gan-an bí àwọn ọmọ ogun tó yí ọ̀págun wọn ká.+
Irun rẹ dà bí agbo ewúrẹ́
Tó ń rọ́ bọ̀ láti gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ Gílíádì.+
6 Eyín rẹ dà bí agbo àgùntàn,
Tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ wẹ̀ fún,
Gbogbo wọn bí ìbejì,
Ọmọ ìkankan nínú wọn ò sì sọ nù.
7 Àwọn ẹ̀rẹ̀kẹ́* rẹ rí bí awẹ́ pómégíránétì
Lábẹ́ aṣọ tí o fi bojú.
9 Àmọ́ ọ̀kan ṣoṣo ni àdàbà mi,+ onítèmi tí ẹwà rẹ̀ ò lábùlà.
Ọ̀kan ṣoṣo tí ìyá rẹ̀ ní.
Òun ni ààyò* ẹni tó bí i.
Àwọn ọmọbìnrin rí i, wọ́n sì ń pè é ní aláyọ̀;
Àwọn ayaba àti wáhàrì rí i, wọ́n sì ń yìn ín.
10 ‘Ta ni obìnrin yìí tó ń tàn* bí ìmọ́lẹ̀ òwúrọ̀,
Tó lẹ́wà bí òṣùpá àrànmọ́jú,
Tó mọ́ rekete bí ìmọ́lẹ̀ oòrùn,
Tó gbayì gan-an bí àwọn ọmọ ogun tó yí ọ̀págun wọn ká?’”+
11 “Mo lọ sínú ọgbà igi eléso,+
Kí n lè rí ohun tó ṣẹ̀ṣẹ̀ hù ní àfonífojì,
Kí n lè rí i bóyá àjàrà ti hù,*
Bóyá àwọn igi pómégíránétì ti yọ òdòdó.
13 “Pa dà wá, pa dà wá, Ṣúlámáítì!
Pa dà wá, pa dà wá,
Ká lè máa wò ẹ́!”
“Kí ló dé tí ẹ̀ ń wo Ṣúlámáítì?”+
“Ó dà bí ijó àwùjọ méjì!”*
7 “Ẹsẹ̀ rẹ mà dára nínú bàtà rẹ o,
Ìwọ ọmọbìnrin tó níwà ọmọlúwàbí!
Àwọn ẹ̀gbẹ̀ẹ̀gbẹ́ itan rẹ dà bí ohun ọ̀ṣọ́,
Iṣẹ́ ọwọ́ oníṣẹ́ ọnà.
2 Ìdodo rẹ dà bí abọ́ roboto.
Kí àdàlù wáìnì má ṣe tán níbẹ̀.
Ikùn rẹ dà bí òkìtì àlìkámà,*
Tí àwọn òdòdó lílì yí ká.
3 Ọmú rẹ méjèèjì dà bí ọmọ àgbọ̀nrín méjì,
Ó dà bí ọmọ egbin tí wọ́n jẹ́ ìbejì.+
4 Ọrùn rẹ+ dà bí ilé gogoro+ tí wọ́n fi eyín erin kọ́.
Imú rẹ dà bí ilé gogoro Lẹ́bánónì,
Tó dojú kọ Damásíkù.
Irun orí rẹ tó gùn ń dá ọba lọ́rùn.*
6 O mà lẹ́wà o, o mà wuni o,
Ìwọ obìnrin tí mo nífẹ̀ẹ́, o wuni ju gbogbo nǹkan dáradára míì!
8 Mo sọ pé, ‘Màá gun igi ọ̀pẹ lọ,
Kí n lè di àwọn ẹ̀ka tí èso rẹ̀ so mọ́ mú.’
Kí ọmú rẹ dà bí òṣùṣù èso àjàrà,
Kí èémí rẹ máa ta sánsán bí àwọn èso ápù,
9 Kí ẹnu* rẹ sì dà bíi wáìnì tó dára jù.”
“Kó máa lọ tìnrín ní ọ̀fun olólùfẹ́ mi,
Bó ṣe rọra ń ṣàn lórí ètè àwọn tó ń sùn.”
10 Olólùfẹ́ mi ló ni mí,+
Èmi sì ni ọkàn rẹ̀ ń fà sí.
12 Jẹ́ ká tètè jí, ká sì lọ sínú àwọn ọgbà àjàrà,
Ká lọ wò ó bóyá àjàrà ti hù,*
Ibẹ̀ ni màá ti fi ìfẹ́ hàn sí ọ.+
Èyí tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ ká àti èyí tí wọ́n ti ká tẹ́lẹ̀,
Ni mo kó pa mọ́ fún ọ, ìwọ olólùfẹ́ mi.
8 “Ká ní o dà bí arákùnrin mi ni,
Tó mu ọmú ìyá mi!
Tí mo bá rí ọ níta, ṣe ni ǹ bá fi ẹnu kò ọ́ lẹ́nu,+
Àwọn èèyàn ò sì ní fi ojú àbùkù wò mí.
Màá fún ọ ní wáìnì tó ń ta sánsán mu,
Omi èso pómégíránétì tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ fún.
3 Ọwọ́ òsì rẹ̀ yóò wà lábẹ́ orí mi,
Á sì fi ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ gbá mi mọ́ra.+
4 Mo mú kí ẹ búra, ẹ̀yin ọmọbìnrin Jerúsálẹ́mù:
Pé kí ẹ má ṣe ta ìfẹ́ jí, ẹ má sì ru ìfẹ́ sókè nínú mi, títí á fi wá fúnra rẹ̀.”+
5 “Ta nìyí, tó ń bọ̀ látinú aginjù,
Tó fara ti olólùfẹ́ rẹ̀?”
“Mo jí ọ lábẹ́ igi ápù.
Ibẹ̀ ni ìyá rẹ ti rọbí nígbà tó fẹ́ bí ọ.
Ibẹ̀ ni ẹni tó bí ọ ti rọbí.
6 Gbé mi lé ọkàn rẹ bí èdìdì,
Bí èdìdì ní apá rẹ,
Torí ìfẹ́ lágbára bí ikú,+
Ìṣòtítọ́ sì lágbára bí Isà Òkú.*
Ọwọ́ iná rẹ̀ dà bí iná tó ń jó, ọwọ́ iná Jáà.*+
Tí ọkùnrin kan bá fi gbogbo ọrọ̀ ilé rẹ̀ fúnni torí ìfẹ́,
Wọ́n á fojú àbùkù wò ó.”*
8 “A ní àbúrò obìnrin kan+
Tí kò tíì ní ọmú.
Kí la máa ṣe fún àbúrò wa
Ní ọjọ́ tí wọ́n bá wá tọrọ rẹ̀?”
9 “Tó bá jẹ́ ògiri,
A ó mọ odi fàdákà sórí rẹ̀,
Àmọ́ tó bá jẹ́ ilẹ̀kùn,
A ó fi pákó kédárì dí i pa.”
10 “Ògiri ni mí,
Ọmú mi sì dà bí ilé gogoro.
Lójú rẹ̀, mo ti wá dà bí
Ẹni tó ní àlàáfíà.
11 Sólómọ́nì ní ọgbà àjàrà+ kan ní Baali-hámọ́nì.
Ó gbé ọgbà àjàrà náà fún àwọn tí á máa tọ́jú rẹ̀.
Kálukú wọn á máa mú ẹgbẹ̀rún (1,000) ẹyọ fàdákà wá fún èso rẹ̀.
12 Mo ní ọgbà àjàrà tèmi.
Sólómọ́nì, ìwọ lo ni ẹgbẹ̀rún (1,000) ẹyọ fàdákà náà,
Igba (200) sì ni ti àwọn tó ń bójú tó èso rẹ̀.”
13 “Ìwọ tí ò ń gbé inú àwọn ọgbà,+
Àwọn ọ̀rẹ́ fẹ́ gbọ́ ohùn rẹ.
Jẹ́ kí n gbọ́ ọ.”+
14 “Tètè, olólùfẹ́ mi,
Kí o sì yára bí egbin+
Tàbí akọ ọmọ àgbọ̀nrín
Lórí àwọn òkè tó ní ewé tó ń ta sánsán.”
Tàbí “Orin tó dùn jù lọ.”
Ní Héb., “Fà mí lọ́wọ́.”
Tàbí “sọ.”
Ìyẹn, àwọn ọ̀dọ́bìnrin.
Tàbí “tí ọkàn mi fẹ́.”
Tàbí “tó lo aṣọ ọ̀fọ̀ tí wọ́n fi ń bojú.”
Tàbí “abo ẹṣin mi.”
Tàbí kó jẹ́, “Irun tí o dì.”
Tàbí “ohun ọ̀ṣọ́ tó rí roboto.”
Ní Héb., “Sípíkénádì.”
Tàbí “O dára lọ́mọkùnrin.”
Tàbí “ilé ńlá.”
Ní Héb., “ilé wáìnì.”
Tàbí “wíńdò.”
Tàbí “Ìgbà òjò.”
Ní Héb., “Títí ọjọ́ á fi bẹ̀rẹ̀ sí í mí.”
Tàbí kó jẹ́, “àwọn òkè tó ní àlàfo.” Tàbí “àwọn òkè Bétérì.”
Tàbí “tí ọkàn mi fẹ́.”
Tàbí “tí ọkàn mi fẹ́.”
Tàbí “ẹni tí ọkàn mi fẹ́.”
Tàbí “ẹni tí ọkàn mi fẹ́.”
Àga tí wọ́n fi nǹkan bò lórí, tí wọ́n fi ń gbé èèyàn pàtàkì.
Tàbí “adé tí wọ́n fi òdòdó hun.”
Tàbí “Ẹ̀bátí.”
Tàbí “apata ribiti.”
Ní Héb., “Títí ọjọ́ yóò fi bẹ̀rẹ̀ sí í mí.”
Tàbí “Òkè Lẹ́bánónì Kejì.”
Tàbí kó jẹ́, “Awọ.”
Tàbí “párádísè pómégíránétì.”
Esùsú tó ń ta sánsán.
Tàbí “Fẹ́ yẹ́ẹ́.”
Tàbí “Mo fẹ́rẹ̀ẹ́ dá kú.”
Tàbí kó jẹ́, “Mo fẹ́rẹ̀ẹ́ dá kú nígbà tó sọ̀rọ̀.”
Tàbí “aṣọ ìbòjú.”
Tàbí kó jẹ́, “dà bí òṣùṣù èso déètì.”
Tàbí kó jẹ́, “létí orísun omi.”
Ní Héb., “Òkè ẹnu.”
Tàbí “Ìlú Tó Wuni.”
Tàbí “ẹ̀bátí.”
Tàbí “ìyàwó onípò kejì.” Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀, “Wáhàrì.”
Ní Héb., “ẹni mímọ́.”
Ní Héb., “tó ń sọ̀ kalẹ̀.”
Tàbí “yọ ìtànná.”
Tàbí “Ọkàn mi.”
Tàbí “tó fẹ́ yọ̀ǹda ara wọn.”
Tàbí “ijó Máhánáímù.”
Tàbí “wíìtì.”
Ní Héb., “Orí rẹ.”
Tàbí “ń mú ọba mọ́lẹ̀.”
Ní Héb., “òkè ẹnu.”
Tàbí “yọ ìtànná.”
Tàbí “Ṣìọ́ọ̀lù,” ìyẹn ibojì aráyé. Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.
“Jáà” ni ìkékúrú Jèhófà.
Tàbí kó jẹ́, “wo ọkùnrin náà.”