ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • nwt Gálátíà 1:1-6:18
  • Gálátíà

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Gálátíà
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
Gálátíà

SÍ ÀWỌN ARÁ GÁLÁTÍÀ

1 Pọ́ọ̀lù, àpọ́sítélì, tí kì í ṣe látọwọ́ àwọn èèyàn tàbí nípasẹ̀ èèyàn kan, bí kò ṣe nípasẹ̀ Jésù Kristi+ àti Ọlọ́run tó jẹ́ Baba,+ ẹni tó gbé e dìde kúrò nínú ikú 2 àti gbogbo àwọn ará tó wà pẹ̀lú mi, sí àwọn ìjọ tó wà ní Gálátíà:

3 Kí inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí àti àlàáfíà látọ̀dọ̀ Ọlọ́run, Baba wa àti Jésù Kristi Olúwa wà pẹ̀lú yín. 4 Ó fi ara rẹ̀ lélẹ̀ nítorí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa,+ kó lè gbà wá sílẹ̀ nínú ètò àwọn nǹkan* búburú ìsinsìnyí,+ gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ Ọlọ́run àti Baba wa,+ 5 ẹni tí ògo jẹ́ tirẹ̀ títí láé àti láéláé. Àmín.

6 Ó yà mí lẹ́nu pé ẹ ti sáré yà kúrò* lọ́dọ̀ Ẹni tó fi inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Kristi pè yín, ẹ sì ń lọ sínú oríṣi ìhìn rere míì.+ 7 Kì í kúkú ṣe pé ìhìn rere míì wà; àmọ́ àwọn kan wà tó ń dá wàhálà sílẹ̀ fún yín,+ tí wọ́n sì fẹ́ yí ìhìn rere nípa Kristi po. 8 Àmọ́ ṣá o, bí àwa tàbí áńgẹ́lì kan láti ọ̀run bá kéde ohun kan fún yín pé ó jẹ́ ìhìn rere, àmọ́ tó yàtọ̀ sí ìhìn rere tí a ti kéde fún yín, kí ó di ẹni ègún. 9 Bí a ṣe sọ ṣáájú, mo tún ń sọ ọ́ báyìí pé, Ẹnikẹ́ni tí ì báà jẹ́ tó bá ń kéde ohun kan fún yín pé ó jẹ́ ìhìn rere, àmọ́ tó yàtọ̀ sí ìhìn rere tí ẹ ti gbà, kí ó di ẹni ègún.

10 Ṣé ojú rere èèyàn ni mò ń wá báyìí ni àbí ti Ọlọ́run? Àbí ìfẹ́ èèyàn ni mo fẹ́ ṣe? Tó bá jẹ́ pé ìfẹ́ èèyàn ni mo ṣì ń ṣe, á jẹ́ pé èmi kì í ṣe ẹrú Kristi. 11 Ẹ̀yin ará, mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ pé ìhìn rere tí mo kéde fún yín kì í ṣe látọ̀dọ̀ èèyàn;+ 12 nítorí mi ò gbà á lọ́wọ́ èèyàn, bẹ́ẹ̀ ni a ò fi kọ́ mi, àmọ́ ó jẹ́ nípasẹ̀ ìfihàn látọwọ́ Jésù Kristi.

13 Ẹ ti gbọ́ nípa ìwà mi tẹ́lẹ̀ nínú Ìsìn Àwọn Júù,+ pé mò ń ṣe inúnibíni tó gbóná* sí ìjọ Ọlọ́run, mo sì ń dà á rú;+ 14 mò ń tẹ̀ síwájú nínú Ìsìn Àwọn Júù ju ọ̀pọ̀ nínú àwọn tí a jọ jẹ́ ẹgbẹ́ lórílẹ̀-èdè mi, torí mo ní ìtara púpọ̀ fún àṣà àwọn baba mi.+ 15 Àmọ́ nígbà tí Ọlọ́run, ẹni tó yọ mí nínú ikùn ìyá mi, tó sì pè mí nípasẹ̀ inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí rẹ̀,+ rí i pé ó dára 16 láti ṣí Ọmọ rẹ̀ payá nípasẹ̀ mi, kí n lè kéde ìhìn rere nípa rẹ̀ fún àwọn orílẹ̀-èdè,+ mi ò lọ fọ̀rọ̀ lọ ẹnikẹ́ni* lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀; 17 bẹ́ẹ̀ ni mi ò lọ sí Jerúsálẹ́mù lọ́dọ̀ àwọn tó jẹ́ àpọ́sítélì ṣáájú mi, àmọ́ mo lọ sí Arébíà, lẹ́yìn náà, mo pa dà sí Damásíkù.+

18 Ọdún mẹ́ta lẹ́yìn náà, mo lọ sí Jerúsálẹ́mù+ lọ́dọ̀ Kéfà,*+ mo sì lo ọjọ́ mẹ́ẹ̀ẹ́dógún (15) lọ́dọ̀ rẹ̀. 19 Àmọ́ mi ò rí ìkankan nínú àwọn àpọ́sítélì yòókù, àfi Jémíìsì+ àbúrò Olúwa. 20 Ní ti àwọn ohun tí mò ń kọ sí yín, mo fi dá yín lójú níwájú Ọlọ́run pé mi ò parọ́.

21 Lẹ́yìn ìyẹn, mo lọ sí agbègbè Síríà àti ti Sìlíṣíà.+ 22 Àmọ́ àwọn ìjọ Jùdíà tó wà ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú Kristi kò dá mi mọ̀. 23 Wọ́n kàn máa ń gbọ́ pé: “Ọkùnrin tó ń ṣe inúnibíni sí wa tẹ́lẹ̀+ ti ń kéde ìhìn rere nípa ẹ̀sìn* tí òun fúnra rẹ̀ ń gbógun tì tẹ́lẹ̀.”+ 24 Torí náà, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í yin Ọlọ́run lógo nítorí mi.

2 Ọdún mẹ́rìnlá (14) lẹ́yìn náà, mo tún lọ sí Jerúsálẹ́mù pẹ̀lú Bánábà,+ mo sì mú Títù dání.+ 2 Mo lọ nítorí ìfihàn kan tí mo rí, mo sì sọ ìhìn rere tí mò ń wàásù láàárín àwọn orílẹ̀-èdè fún wọn. Àmọ́, ó jẹ́ níkọ̀kọ̀, níwájú àwọn èèyàn pàtàkì,* kí n lè rí i dájú pé eré tí mò ń sá tàbí èyí tí mo ti sá kì í ṣe lásán. 3 Bó tiẹ̀ jẹ́ pé Gíríìkì ni Títù+ tó wà pẹ̀lú mi, wọn ò fi dandan mú un pé kó dádọ̀dọ́.*+ 4 Àmọ́ ọ̀rọ̀ yìí jẹyọ nítorí àwọn èké arákùnrin tó wọlé ní bòókẹ́lẹ́,+ àwọn tó yọ́ wọlé láti ṣe amí òmìnira+ tí a ní nínú Kristi Jésù, kí wọ́n lè sọ wá di ẹrú pátápátá;+ 5 a kò gbà fún wọn,+ rárá o, kì í tiẹ̀ ṣe fún ìṣẹ́jú* kan, kí òtítọ́ ìhìn rere lè máa wà pẹ̀lú yín.

6 Àmọ́ ní ti àwọn tó dà bíi pé wọ́n ṣe pàtàkì,+ irú ẹni tí wọ́n jẹ́ tẹ́lẹ̀ kò jẹ́ nǹkan kan lójú mi, torí Ọlọ́run kì í wo bí ẹnì kan ṣe rí lóde, kò sí ohun tuntun kankan tí àwọn tó gbayì yẹn kọ́ mi. 7 Dípò bẹ́ẹ̀, nígbà tí wọ́n rí i pé a ti fi sí ìkáwọ́ mi láti sọ ìhìn rere fún àwọn tó jẹ́ aláìdádọ̀dọ́,*+ gẹ́gẹ́ bí a ṣe fi sí ìkáwọ́ Pétérù láti sọ ọ́ fún àwọn tó dádọ̀dọ́,* 8 nítorí ẹni tó fún Pétérù lágbára láti ṣe iṣẹ́ àpọ́sítélì láàárín àwọn tó dádọ̀dọ́, fún èmi náà lágbára láti ṣe é láàárín àwọn èèyàn orílẹ̀-èdè,+ 9 nígbà tí wọ́n rí inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí tí a fún mi,+ Jémíìsì+ àti Kéfà* àti Jòhánù, àwọn tó dà bí òpó nínú ìjọ, bọ èmi àti Bánábà+ lọ́wọ́ láti fi hàn pé wọ́n fara mọ́ ọn pé* kí a lọ sọ́dọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè, kí àwọn sì lọ sọ́dọ̀ àwọn tó dádọ̀dọ́. 10 Ohun kan ṣoṣo tí wọ́n béèrè ni pé kí a fi àwọn aláìní sọ́kàn, mo sì ń sapá gan-an láti ṣe bẹ́ẹ̀.+

11 Àmọ́ ṣá o, nígbà tí Kéfà*+ wá sí Áńtíókù,+ mo ta kò ó lójúkojú,* nítorí ó ṣe kedere pé ohun tó ṣe kò tọ́.* 12 Torí kí àwọn kan látọ̀dọ̀ Jémíìsì+ tó dé, ó máa ń bá àwọn èèyàn orílẹ̀-èdè jẹun;+ àmọ́ nígbà tí wọ́n dé, kò ṣe bẹ́ẹ̀ mọ́, ó sì ya ara rẹ̀ sọ́tọ̀, torí ó ń bẹ̀rù àwọn tó dádọ̀dọ́.*+ 13 Àwọn Júù yòókù náà dara pọ̀ mọ́ ọn láti máa díbọ́n,* débi pé Bánábà pàápàá bẹ̀rẹ̀ sí í bá wọn díbọ́n.* 14 Àmọ́ nígbà tí mo rí i pé wọn kò rìn lọ́nà tó bá òtítọ́ ìhìn rere mu,+ mo sọ fún Kéfà* níṣojú gbogbo wọn pé: “Bí ìwọ tí o jẹ́ Júù, bá ń gbé ìgbé ayé àwọn èèyàn orílẹ̀-èdè, tí o kò ṣe bíi ti àwọn Júù, kí ló wá dé tí o fi ń sọ ọ́ di dandan pé kí àwọn èèyàn orílẹ̀-èdè máa tẹ̀ lé àṣà àwọn Júù?”+

15 Àwa tí wọ́n bí ní Júù, tí a kì í ṣe ẹlẹ́ṣẹ̀ látinú àwọn orílẹ̀-èdè, 16 mọ̀ pé kì í ṣe àwọn iṣẹ́ òfin ló ń mú ká pe èèyàn ní olódodo, bí kò ṣe nípasẹ̀ ìgbàgbọ́+ nínú Jésù Kristi+ nìkan. Ìdí nìyẹn tí a fi ní ìgbàgbọ́ nínú Kristi Jésù, kí a lè pè wá ní olódodo nípasẹ̀ ìgbàgbọ́ nínú Kristi, kì í ṣe nípasẹ̀ àwọn iṣẹ́ òfin, nítorí kò sí ẹni* tí a máa pè ní olódodo nípasẹ̀ àwọn iṣẹ́ òfin.+ 17 Ní báyìí, tí wọ́n bá ń rí wa ní ẹlẹ́ṣẹ̀ níbi tí a ti ń wá bí Ọlọ́run ṣe máa pè wá ní olódodo nípasẹ̀ Kristi, ṣé Kristi wá jẹ́ òjíṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ ni? Ká má ri! 18 Tó bá jẹ́ pé àwọn ohun tí mo ti wó lulẹ̀ rí ni mo tún ń gbé ró, ṣe ni mò ń fi hàn pé arúfin ni mí. 19 Torí nípasẹ̀ òfin, mo ti di òkú sí òfin,+ kí n lè di alààyè sí Ọlọ́run. 20 Wọ́n ti kàn mí mọ́gi pẹ̀lú Kristi.+ Kì í ṣe èmi ló wà láàyè mọ́,+ Kristi ló wà láàyè nínú mi. Ní tòótọ́, ìgbésí ayé tí mò ń gbé báyìí nínú ara ni mò ń gbé nípasẹ̀ ìgbàgbọ́ nínú Ọmọ Ọlọ́run,+ ẹni tó nífẹ̀ẹ́ mi, tó sì fi ara rẹ̀ lélẹ̀ fún mi.+ 21 Mi ò kọ inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Ọlọ́run,*+ nítorí tí òdodo bá jẹ́ nípasẹ̀ òfin, á jẹ́ pé lásán ni Kristi kú.+

3 Ẹ̀yin aláìnírònú ará Gálátíà! Ta ló tàn yín sínú ìwà ibi yìí,+ ẹ̀yin tó hàn sí kedere pé a kan Jésù Kristi mọ́gi?+ 2 Ohun kan tí mo fẹ́ bi yín* ni pé: Ṣé ipasẹ̀ àwọn iṣẹ́ òfin lẹ fi gba ẹ̀mí ni àbí nítorí pé ẹ nígbàgbọ́ nínú ohun tí ẹ gbọ́?+ 3 Ṣé bẹ́ẹ̀ lẹ ya aláìnírònú tó ni? Lẹ́yìn tí ẹ ti bẹ̀rẹ̀ ní ọ̀nà ti ẹ̀mí,* ṣé ẹ fẹ́ parí ní ọ̀nà ti ara ni?*+ 4 Ṣé lásán lẹ jẹ ìyà tó pọ̀ tó bẹ́ẹ̀ ni? Mi ò gbà pé lásán ni. 5 Nítorí náà, ṣé ẹni tó ń fún yín ní ẹ̀mí, tó sì ń ṣe àwọn iṣẹ́ agbára+ láàárín yín ń ṣe é torí àwọn iṣẹ́ òfin ni àbí nítorí ìgbàgbọ́ tí ẹ ní nínú ohun tí ẹ gbọ́? 6 Gẹ́gẹ́ bí Ábúráhámù ṣe “ní ìgbàgbọ́ nínú Jèhófà,* tí a sì kà á sí òdodo fún un.”+

7 Ẹ kúkú mọ̀ pé àwọn tó rọ̀ mọ́ ìgbàgbọ́ ni ọmọ Ábúráhámù.+ 8 Bí ìwé mímọ́ ṣe rí i ṣáájú pé Ọlọ́run máa pe àwọn èèyàn àwọn orílẹ̀-èdè ní olódodo nípasẹ̀ ìgbàgbọ́, ó kéde ìhìn rere náà fún Ábúráhámù ṣáájú pé: “Ipasẹ̀ rẹ ni gbogbo orílẹ̀-èdè yóò fi rí ìbùkún gbà.”+ 9 Nítorí náà, àwọn tó ń rọ̀ mọ́ ìgbàgbọ́ ń rí ìbùkún gbà pẹ̀lú Ábúráhámù tó ní ìgbàgbọ́.+

10 Gbogbo àwọn tó gbára lé àwọn iṣẹ́ òfin wà lábẹ́ ègún, nítorí ó wà lákọsílẹ̀ pé: “Ègún ni fún gbogbo ẹni tí kò bá dúró nínú gbogbo ohun tó wà lákọsílẹ̀ nínú àkájọ ìwé Òfin láti pa wọ́n mọ́.”+ 11 Yàtọ̀ síyẹn, ó ṣe kedere pé kò sí ẹnì kankan tí a pè ní olódodo lọ́dọ̀ Ọlọ́run nípasẹ̀ òfin,+ nítorí “ìgbàgbọ́ yóò mú kí olódodo wà láàyè.”+ 12 Òfin kò dá lórí ìgbàgbọ́. Àmọ́, “yóò mú kí ẹni tó bá ń pa àwọn ohun tó sọ mọ́ wà láàyè.”+ 13 Kristi rà wá,+ ó tú wa sílẹ̀+ lábẹ́ ègún Òfin bó ṣe di ẹni ègún dípò wa, nítorí ó wà lákọsílẹ̀ pé: “Ẹni ègún ni ẹni tí a gbé kọ́ sórí òpó igi.”+ 14 Èyí jẹ́ nítorí kí ìbùkún Ábúráhámù lè dé ọ̀dọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè nípasẹ̀ Kristi Jésù,+ kí a lè rí ẹ̀mí tí Ọlọ́run ṣèlérí+ gbà nípasẹ̀ ìgbàgbọ́ wa.

15 Ẹ̀yin ará, mo fẹ́ fi ohun kan tí àwa èèyàn máa ń ṣe ṣàpèjúwe fún yín: Tí a bá ti fìdí májẹ̀mú kan múlẹ̀, kódà kó jẹ́ látọwọ́ ẹnì kan, kò sí ẹni tó lè fagi lé e tàbí kó fi kún un. 16 Àwọn ìlérí náà la sọ fún Ábúráhámù àti fún ọmọ* rẹ̀.+ Kò sọ pé, “àti fún àwọn ọmọ* rẹ,” bíi pé wọ́n pọ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó sọ pé, “àti fún ọmọ* rẹ,” ìyẹn ẹnì kan ṣoṣo, tó jẹ́ Kristi.+ 17 Síwájú sí i, mo sọ èyí pé: Òfin tó dé ní ọgọ́rùn-ún mẹ́rin ó lé ọgbọ̀n (430) ọdún lẹ́yìn náà+ kò fagi lé májẹ̀mú tí Ọlọ́run ti dá, tó fi máa fòpin sí ìlérí náà. 18 Torí tí ogún náà bá dá lórí òfin, kò dá lórí ìlérí mọ́ nìyẹn; àmọ́ Ọlọ́run ti fún Ábúráhámù ní ogún náà nípasẹ̀ ìlérí nítorí inú rere òun fúnra rẹ̀.+

19 Ti Òfin ti wá jẹ́? A fi kún un láti mú kí àwọn àṣìṣe fara hàn kedere,+ títí ọmọ* tí a ṣe ìlérí náà fún á fi dé;+ a sì fi í rán àwọn áńgẹ́lì  + nípasẹ̀ alárinà kan.+ 20 Kì í sí alárinà níbi tó bá ti jẹ́ pé ẹnì kan ṣoṣo ni ọ̀rọ̀ kàn, ẹnì kan ṣoṣo sì ni Ọlọ́run. 21 Ṣé Òfin wá ta ko àwọn ìlérí Ọlọ́run ni? Kò rí bẹ́ẹ̀ rárá! Torí ká ní òfin tí a fún wa lè fúnni ní ìyè ni, òdodo ì bá ti wá nípasẹ̀ òfin. 22 Àmọ́ Ìwé Mímọ́ fi ohun gbogbo sínú àhámọ́ ẹ̀ṣẹ̀, kí àwọn tó ní ìgbàgbọ́ lè gba ìlérí tó ń wá látinú ìgbàgbọ́ nínú Jésù Kristi.

23 Àmọ́ ṣá o, kí ìgbàgbọ́ náà tó dé, à ń ṣọ́ wa lábẹ́ òfin, à ń fi wá sínú àhámọ́, a sì ń retí ìgbàgbọ́ tí Ọlọ́run máa tó ṣí payá.+ 24 Nítorí náà, Òfin di olùtọ́* wa tó ń sinni lọ sọ́dọ̀ Kristi,+ kí a lè pè wá ní olódodo nípasẹ̀ ìgbàgbọ́.+ 25 Àmọ́ ní báyìí tí ìgbàgbọ́ ti dé,+ a ò sí lábẹ́ olùtọ́* kankan mọ́.+

26 Ní tòótọ́, ọmọ Ọlọ́run ni gbogbo yín+ nípasẹ̀ ìgbàgbọ́ yín nínú Kristi Jésù.+ 27 Nítorí gbogbo ẹ̀yin tí a ti batisí sínú Kristi ti gbé Kristi wọ̀.+ 28 Kò tún sí pé ẹnì kan jẹ́ Júù tàbí Gíríìkì,+ ẹrú tàbí òmìnira,+ ọkùnrin tàbí obìnrin,+ nítorí ọ̀kan ṣoṣo ni gbogbo yín nínú Kristi Jésù.+ 29 Yàtọ̀ síyẹn, bí ẹ bá jẹ́ ti Kristi, ẹ jẹ́ ọmọ* Ábúráhámù lóòótọ́,+ ajogún+ nípasẹ̀ ìlérí.+

4 Ní báyìí, mo sọ pé nígbà tí ajogún náà bá ṣì jẹ́ ọmọdé, kò yàtọ̀ sí ẹrú, bó tilẹ̀ jẹ́ olúwa ohun gbogbo, 2 àmọ́ ó wà lábẹ́ àwọn alábòójútó àti àwọn ìríjú títí di ọjọ́ tí bàbá rẹ̀ ti yàn. 3 Bákan náà, ní tiwa, nígbà tí a wà lọ́mọdé, àwọn èrò àti ìṣe ayé* ń mú wa lẹ́rú.+ 4 Àmọ́ nígbà tí àkókò tó, Ọlọ́run rán Ọmọ rẹ̀, ẹni tí obìnrin bí,+ tí ó sì wà lábẹ́ òfin,+ 5 kí ó lè ra àwọn tó wà lábẹ́ òfin,+ kí ó sì tipa bẹ́ẹ̀ tú wọn sílẹ̀, kí a lè rí ìsọdọmọ gbà.+

6 Nítorí pé ẹ jẹ́ ọmọ, Ọlọ́run ti rán ẹ̀mí+ Ọmọ rẹ̀ sínú ọkàn wa,+ ó sì ń ké jáde pé: “Ábà,* Bàbá!”+ 7 Torí náà, ẹ kì í ṣe ẹrú mọ́, ọmọ ni yín; tí ẹ bá sì jẹ́ ọmọ, ẹ tún jẹ́ ajogún nípasẹ̀ Ọlọ́run.+

8 Síbẹ̀, nígbà tí ẹ kò mọ Ọlọ́run, ẹ̀ ń ṣẹrú àwọn tí kì í ṣe ọlọ́run. 9 Àmọ́ ní báyìí tí ẹ ti mọ Ọlọ́run, tàbí ká kúkú sọ pé, tí Ọlọ́run ti mọ̀ yín, kí ló dé tí ẹ tún ń pa dà sí àwọn ohun àkọ́bẹ̀rẹ̀ tó jẹ́ aláìlera+ àti aláìníláárí,* tí ẹ sì tún fẹ́ ṣẹrú wọn?+ 10 Ẹ̀ ń pa àwọn ọjọ́ àti oṣù+ àti àsìkò àti ọdún mọ́ délẹ̀délẹ̀. 11 Ẹ̀rù ń bà mí nítorí yín, kó má lọ jẹ́ pé lásán ni gbogbo wàhálà tí mo ṣe lórí yín.

12 Ẹ̀yin ará, mo bẹ̀ yín, ẹ dà bí èmi, nítorí èmi náà ti máa ń ṣe bíi tiyín tẹ́lẹ̀.+ Ẹ ò ṣe àìtọ́ kankan sí mi. 13 Ṣùgbọ́n ẹ mọ̀ pé àìsàn tó ṣe mí ló jẹ́ kí n kọ́kọ́ láǹfààní láti kéde ìhìn rere fún yín. 14 Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àdánwò ni àìlera mi jẹ́ fún yín, ẹ ò fojú pa mí rẹ́, ẹ ò sì kórìíra mi;* àmọ́ ṣe lẹ gbà mí bí áńgẹ́lì Ọlọ́run, bíi Kristi Jésù. 15 Ibo ni ayọ̀ tí ẹ ní tẹ́lẹ̀ wà? Nítorí mo jẹ́rìí yín pé, ká ló ṣeé ṣe ni, ẹ lè yọ ojú yín fún mi.+ 16 Ṣé mo ti wá di ọ̀tá yín torí pé mo sọ òótọ́ fún yín ni? 17 Àwọn kan ń wá ọ̀nà lójú méjèèjì láti fà yín sábẹ́ ara wọn, àmọ́ kì í ṣe fún ire yín; ṣe ni wọ́n fẹ́ fà yín kúrò lọ́dọ̀ mi, kó lè máa yá yín lára láti tẹ̀ lé wọn. 18 Síbẹ̀, ó dáa tí ẹnì kan bá ń wá yín lójú méjèèjì fún ire yín, tí kì í ṣe nígbà tí mo bá wà lọ́dọ̀ yín nìkan, 19 ẹ̀yin ọmọ mi kéékèèké,+ tí mo tún tìtorí yín wà nínú ìrora ìbímọ títí ẹ ó fi lè gbé Kristi yọ* nínú yín. 20 Ó wù mí kí n wà lọ́dọ̀ yín ní báyìí, kí n sì sọ̀rọ̀ lọ́nà tó yàtọ̀, torí ọkàn mi ń dààmú nítorí yín.

21 Ẹ sọ fún mi, ẹ̀yin tí ẹ fẹ́ wà lábẹ́ òfin, Ṣé ẹ ò gbọ́ ohun tí Òfin sọ ni? 22 Bí àpẹẹrẹ, ó wà lákọsílẹ̀ pé Ábúráhámù ní ọmọkùnrin méjì, ọ̀kan látọ̀dọ̀ ìránṣẹ́bìnrin,+ èkejì látọ̀dọ̀ obìnrin tó lómìnira;+ 23 àmọ́ èyí tí ìránṣẹ́bìnrin bí jẹ́ lọ́nà ti ẹ̀dá,*+ èyí tí obìnrin tó lómìnira sì bí jẹ́ nípasẹ̀ ìlérí.+ 24 A lè fi àwọn nǹkan yìí ṣe àkàwé; àwọn obìnrin yìí dúró fún májẹ̀mú méjì, èyí tó wá láti Òkè Sínáì,+ tó ń bí ọmọ fún ìsìnrú, ni Hágárì. 25 Hágárì dúró fún Sínáì,+ òkè kan ní Arébíà, ó sì ṣe rẹ́gí pẹ̀lú Jerúsálẹ́mù ti òní, torí ó ń ṣẹrú pẹ̀lú àwọn ọmọ rẹ̀. 26 Àmọ́ Jerúsálẹ́mù ti òkè ní òmìnira, òun sì ni ìyá wa.

27 Nítorí ó wà lákọsílẹ̀ pé: “Máa yọ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀, ìwọ àgàn tí kò bímọ; bú sígbe ayọ̀, ìwọ obìnrin tí kò ní ìrora ìbímọ; nítorí àwọn ọmọ obìnrin tó ti di ahoro pọ̀ ju ti obìnrin tó ní ọkọ lọ.”+ 28 Tóò, ẹ̀yin ará, ẹ̀yin náà jẹ́ ọmọ ìlérí bí Ísákì ṣe jẹ́.+ 29 Àmọ́ bó ṣe rí nígbà yẹn tí èyí tí a bí lọ́nà ti ẹ̀dá* bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe inúnibíni sí èyí tí a bí lọ́nà ti ẹ̀mí,+ bẹ́ẹ̀ náà ló ṣe rí ní báyìí.+ 30 Síbẹ̀, kí ni ìwé mímọ́ sọ? “Lé ìránṣẹ́bìnrin náà àti ọmọkùnrin rẹ̀ jáde, nítorí ọmọ ìránṣẹ́bìnrin náà kò ní bá ọmọ obìnrin tó lómìnira pín ogún lọ́nàkọnà.”+ 31 Nítorí náà, ẹ̀yin ará, a kì í ṣe ọmọ ìránṣẹ́bìnrin, ọmọ obìnrin tó lómìnira ni wá.

5 Kristi ti dá wa sílẹ̀ ká lè ní irú òmìnira yìí. Nítorí náà, ẹ dúró gbọn-in,+ ẹ má sì tọrùn bọ àjàgà ẹrú mọ́.+

2 Ẹ wò ó! Èmi, Pọ́ọ̀lù, ń sọ fún yín pé tí ẹ bá dádọ̀dọ́,* Kristi ò ní ṣe yín láǹfààní kankan.+ 3 Mo tún jẹ́rìí sí i pé dandan ni fún gbogbo ẹni tó bá dádọ̀dọ́* láti pa gbogbo Òfin mọ́.+ 4 Ẹ ti kúrò lọ́dọ̀ Kristi, ẹ̀yin tí ẹ fẹ́ kí a pè yín ní olódodo nípasẹ̀ òfin;+ ẹ ti yà kúrò nínú inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí rẹ̀. 5 Ní tiwa, nínú ẹ̀mí, à ń dúró de òdodo tí à ń retí lójú méjèèjì, èyí tó ń wá látinú ìgbàgbọ́. 6 Torí nínú Kristi Jésù, ìdádọ̀dọ́* tàbí àìdádọ̀dọ́* kò ṣàǹfààní,+ ìgbàgbọ́ tó ń ṣiṣẹ́ nípasẹ̀ ìfẹ́ ló ṣàǹfààní.

7 Ẹ ti ń sáré dáadáa tẹ́lẹ̀.+ Ta ló dí yín lọ́wọ́ kí ẹ má ṣègbọràn sí òtítọ́ mọ́? 8 Irú èrò tí wọ́n fi yí yín lọ́kàn pa dà yìí kò wá látọ̀dọ̀ Ẹni tó ń pè yín. 9 Ìwúkàrà díẹ̀ ló ń mú gbogbo ìṣùpọ̀ wú.+ 10 Ọkàn mi balẹ̀ pé ẹ̀yin tí ẹ wà nínú Olúwa+ kò ní ronú lọ́nà míì; àmọ́, ẹni tó ń dá wàhálà sílẹ̀ fún yín,+ ẹnì yòówù kó jẹ́, yóò gba ìdájọ́ tó tọ́ sí i. 11 Ní tèmi, ẹ̀yin ará, tí mo bá ṣì ń wàásù ìdádọ̀dọ́,* kí ló dé tí wọ́n tún ń ṣe inúnibíni sí mi? Tó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, òpó igi oró*+ kì í ṣe ohun ìkọ̀sẹ̀ mọ́ fún àwọn tó ń ta kò mí. 12 Ó wù mí kí àwọn tó fẹ́ da àárín yín rú tẹ ara wọn lọ́dàá.*

13 Ẹ̀yin ará, a pè yín kí ẹ lè ní òmìnira; kìkì pé kí ẹ má ṣe lo òmìnira yìí láti máa ṣe ìfẹ́ ti ara,+ àmọ́ ẹ jẹ́ kí ìfẹ́ máa mú kí ẹ sin ara yín bí ẹrú.+ 14 Nítorí a ti mú gbogbo Òfin ṣẹ nínú* àṣẹ kan ṣoṣo, tó sọ pé: “Kí o nífẹ̀ẹ́ ọmọnìkejì rẹ bí ara rẹ.”+ 15 Tí ẹ bá wá ń bu ara yín jẹ, tí ẹ sì ń fa ara yín ya,+ ẹ ṣọ́ra kí ẹ má bàa pa ara yín run.+

16 Àmọ́ mo sọ pé, Ẹ máa rìn nípa ẹ̀mí,+ ẹ kò sì ní ṣe ìfẹ́ ti ara rárá.+ 17 Nítorí ohun tí ara ń fẹ́ lòdì sí ohun tí ẹ̀mí ń fẹ́, ẹ̀mí sì lòdì sí ara; àwọn méjèèjì ta ko ara wọn, ìdí nìyẹn tí ẹ kò fi lè ṣe ohun tí ẹ fẹ́ ṣe.+ 18 Yàtọ̀ síyẹn, tí ẹ̀mí bá ń darí yín, ẹ kò sí lábẹ́ òfin.

19 Àwọn iṣẹ́ ti ara hàn kedere, àwọn sì ni ìṣekúṣe,*+ ìwà àìmọ́, ìwà àìnítìjú,*+ 20 ìbọ̀rìṣà, ìbẹ́mìílò,*+ ìkórìíra, wàhálà, owú, inú fùfù, awuyewuye, ìpínyà, ẹ̀ya ìsìn, 21 ìlara, ìmutíyó,+ àwọn àríyá aláriwo àti irú àwọn nǹkan yìí.+ Mò ń kìlọ̀ fún yín ṣáájú nípa àwọn nǹkan yìí, lọ́nà kan náà tí mo gbà kìlọ̀ fún yín tẹ́lẹ̀, pé àwọn tó bá ń ṣe àwọn nǹkan yìí kò ní jogún Ìjọba Ọlọ́run.+

22 Àmọ́, èso ti ẹ̀mí ni ìfẹ́, ayọ̀, àlàáfíà, sùúrù,* inú rere, ìwà rere,+ ìgbàgbọ́, 23 ìwà tútù, ìkóra-ẹni-níjàánu.+ Kò sí òfin kankan tó lòdì sí irú àwọn nǹkan yìí. 24 Yàtọ̀ síyẹn, àwọn tó jẹ́ ti Kristi Jésù ti kan ẹran ara mọ́gi* pẹ̀lú ohun tí ẹran ara ń fẹ́ àti ohun tó ń wù ú.+

25 Tí a bá wà láàyè nípa ẹ̀mí, ẹ jẹ́ kí a máa rìn létòlétò nípa ẹ̀mí.+ 26 Ẹ má ṣe jẹ́ kí a di agbéraga,+ kí a má ṣe máa bá ara wa díje,+ kí a má sì máa jowú ara wa.

6 Ẹ̀yin ará, tí ẹnì kan bá tiẹ̀ ṣi ẹsẹ̀ gbé kó tó mọ̀, kí ẹ̀yin tí ẹ kúnjú ìwọ̀n nípa tẹ̀mí sapá láti fi pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́* tọ́ ẹni náà sọ́nà.+ Àmọ́ kí ẹ máa kíyè sí ara yín lójú méjèèjì,+ kí a má bàa dẹ ẹ̀yin náà wò.+ 2 Ẹ máa bá ara yín gbé ẹrù tó wúwo,+ nípa bẹ́ẹ̀, ẹ ó mú òfin Kristi ṣẹ.+ 3 Tí ẹnì kan bá rò pé òun jẹ́ nǹkan kan nígbà tí kò jẹ́ nǹkan kan,+ ó ń tan ara rẹ̀ jẹ ni. 4 Àmọ́ kí kálukú máa yẹ ohun tó ń ṣe wò,+ nígbà náà, yóò láyọ̀ nítorí ohun tí òun fúnra rẹ̀ ṣe, kì í ṣe torí pé ó fi ara rẹ̀ wé ẹlòmíì.+ 5 Torí kálukú ló máa ru ẹrù ara rẹ̀.*+

6 Yàtọ̀ síyẹn, kí ẹni tí à ń kọ́* ní ọ̀rọ̀ náà máa ṣàjọpín ohun rere gbogbo pẹ̀lú ẹni tó ń kọ́ni* ní irú ẹ̀kọ́ bẹ́ẹ̀.+

7 Ẹ má ṣe jẹ́ kí ẹnikẹ́ni tàn yín jẹ: Ọlọ́run kò ṣeé tàn.* Nítorí ohun tí èèyàn bá gbìn, òun ló máa ká;+ 8 torí pé ẹni tó bá ń fúnrúgbìn nítorí ara rẹ̀ máa ká ìdíbàjẹ́ látinú ara rẹ̀, àmọ́ ẹni tó bá ń fúnrúgbìn nítorí ẹ̀mí máa ká ìyè àìnípẹ̀kun látinú ẹ̀mí.+ 9 Nítorí náà, ẹ má ṣe jẹ́ kí a jáwọ́ nínú ṣíṣe rere, torí tí àkókò bá tó, a máa kórè rẹ̀ tí a ò bá jẹ́ kó rẹ̀ wá.*+ 10 Tóò, nígbà tí a bá ti láǹfààní rẹ̀,* ẹ jẹ́ ká máa ṣe rere fún gbogbo èèyàn, àmọ́ ní pàtàkì fún àwọn tó bá wa tan nínú ìgbàgbọ́.

11 Ẹ wo àwọn lẹ́tà gàdàgbà tí mo fi kọ̀wé sí yín ní ọwọ́ ara mi.

12 Gbogbo àwọn tí ó fẹ́ kí àwọn èèyàn ní èrò tó dáa nípa wọn nínú ara,* ni àwọn tó fẹ́ sọ ọ́ di dandan fún yín pé kí ẹ dádọ̀dọ́,* wọ́n sì ń ṣe bẹ́ẹ̀ kí a má bàa ṣe inúnibíni sí wọn nítorí òpó igi oró* Kristi. 13 Nítorí àwọn tó ń dádọ̀dọ́* pàápàá kì í pa Òfin mọ́,+ àmọ́ wọ́n fẹ́ kí ẹ dádọ̀dọ́ kí wọ́n lè máa ti ara yín yangàn. 14 Ní tèmi, mi ò ní yangàn láé, àfi nípa òpó igi oró* Olúwa wa Jésù Kristi,+ ẹni tí a tipasẹ̀ rẹ̀ sọ ayé di òkú* lójú tèmi àti èmi lójú ti ayé. 15 Nítorí ìdádọ̀dọ́* tàbí àìdádọ̀dọ́* kọ́ ló ṣe pàtàkì,+ ẹ̀dá tuntun ló ṣe pàtàkì.+ 16 Ní ti gbogbo àwọn tó ń rìn létòlétò nínú ìlànà ìwà rere yìí, kí àlàáfíà àti àánú wà lórí wọn, bẹ́ẹ̀ ni, lórí Ísírẹ́lì Ọlọ́run.+

17 Láti ìsinsìnyí lọ, kí ẹnikẹ́ni má dà mí láàmú mọ́, nítorí àpá ẹrú Jésù wà ní ara mi.+

18 Ẹ̀yin ará, kí inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Olúwa wa Jésù Kristi wà pẹ̀lú ẹ̀mí tí ẹ̀ ń fi hàn. Àmín.

Tàbí “àsìkò.” Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.

Tàbí “a ti sáré mú yín kúrò.”

Ní Grk., “tó dé ìwọ̀n tó pọ̀ lápọ̀jù.”

Ní Grk., “ẹran ara àti ẹ̀jẹ̀.”

Wọ́n tún ń pè é ní Pétérù.

Ní Grk., “ìgbàgbọ́.”

Tàbí “tó gbayì.”

Tàbí “kọlà.”

Ní Grk., “wákàtí.”

Tàbí “aláìkọlà.”

Tàbí “kọlà.”

Wọ́n tún ń pè é ní Pétérù.

Tàbí “fọwọ́ sí i pé ká jọ ṣiṣẹ́.”

Wọ́n tún ń pè é ní Pétérù.

Tàbí “mo wò ó lójú.”

Tàbí “ó yẹ lẹ́ni tí à ń dá lẹ́bi.”

Tàbí “kọlà.”

Tàbí “ṣe àgàbàgebè.”

Tàbí “ṣe àgàbàgebè.”

Wọ́n tún ń pè é ní Pétérù.

Ní Grk., “ẹran ara.”

Tàbí “pa inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Ọlọ́run tì.”

Ní Grk., “mọ̀ lọ́dọ̀ yín.”

Ní Grk., “nínú ẹ̀mí.”

Ní Grk., “ṣé inú ẹran ara lẹ ti fẹ́ parí ni?”

Wo Àfikún A5.

Ní Grk., “èso.”

Ní Grk., “àwọn èso.”

Ní Grk., “èso.”

Ní Grk., “èso.”

Tàbí “olùkọ́.”

Tàbí “olùkọ́.”

Ní Grk., “èso.”

Tàbí “àwọn ohun àkọ́bẹ̀rẹ̀ ayé.”

Ọ̀rọ̀ Hébérù tàbí Árámáíkì tó túmọ̀ sí “Bàbá!”

Tàbí “akúrẹtẹ̀.”

Tàbí “tutọ́ sí mi lára.”

Tàbí “títí Kristi yóò fi di odindi.”

Ní Grk., “ara.”

Ní Grk., “ara.”

Tàbí “kọlà.”

Tàbí “kọlà.”

Tàbí “ìkọlà.”

Tàbí “àìkọlà.”

Tàbí “ìkọlà.”

Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.

Tàbí “di ìwẹ̀fà,” kí wọ́n tipa bẹ́ẹ̀ di ẹni tí kò kúnjú ìwọ̀n láti tẹ̀ lé òfin tí wọ́n fọwọ́ sí.

Tàbí kó jẹ́, “kó gbogbo Òfin jọ sínú.”

Lédè Gíríìkì, por·neiʹa. Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.

Tàbí “ìwà ọ̀dájú.” Ní Gíríìkì, a·selʹgei·a. Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.

Tàbí “iṣẹ́ oṣó; lílo oògùn olóró.”

Tàbí “ìpamọ́ra.”

Tàbí “mọ́ òpó igi.” Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.

Ní Grk., “ẹ̀mí ìwà tútù.”

Tàbí “ṣe ojúṣe tirẹ̀.”

Tàbí “fi ọ̀rọ̀ ẹnu kọ́.”

Tàbí “fi ọ̀rọ̀ ẹnu kọ́ni.”

Ní Grk., “fi ṣe ẹlẹ́yà.”

Tàbí “juwọ́ sílẹ̀.”

Ní Grk., “ní àkókò tí a yàn kalẹ̀.”

Tàbí “tí wọ́n fẹ́ lẹ́wà lóde ara.”

Tàbí “kọlà.”

Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.

Tàbí “kọlà.”

Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.

Tàbí “kan ayé mọ́gi.”

Tàbí “ìkọlà.”

Tàbí “àìkọlà.”

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́