ÉMỌ́SÌ
1 Ọ̀rọ̀ Émọ́sì,* ọ̀kan lára àwọn tó ń sin àgùntàn láti Tékóà,+ èyí tó gbọ́ nínú ìran nípa Ísírẹ́lì nígbà ayé Ùsáyà+ ọba Júdà àti nígbà ayé Jèróbóámù+ ọmọ Jóáṣì,+ ọba Ísírẹ́lì, ní ọdún méjì ṣáájú ìmìtìtì ilẹ̀ tó wáyé.+ 2 Ó sọ pé:
“Jèhófà yóò ké ramúramù láti Síónì,
Yóò sì gbé ohùn rẹ̀ sókè láti Jerúsálẹ́mù.
Ibi ìjẹko àwọn olùṣọ́ àgùntàn máa ṣọ̀fọ̀,
Ewéko orí òkè Kámẹ́lì á sì gbẹ dà nù.”+
3 “Ohun tí Jèhófà sọ nìyí,
‘“Nítorí ìdìtẹ̀* mẹ́ta Damásíkù àti nítorí mẹ́rin, mi ò ní yí ọwọ́ mi pa dà,
Nítorí wọ́n fi ohun èlò ìpakà onírin pa Gílíádì bí ọkà.+
5 Màá ṣẹ́ ọ̀pá ìdábùú ẹnubodè Damásíkù;+
Màá sì pa àwọn tó ń gbé Bikati-áfénì run
Àti àwọn tó ń ṣàkóso* ní Bẹti-édẹ́nì;
Àwọn èèyàn Síríà sì máa lọ sí ìgbèkùn ní Kírì,”+ ni Jèhófà wí.’
6 Ohun tí Jèhófà sọ nìyí,
‘“Nítorí ìdìtẹ̀ mẹ́ta ti Gásà+ àti nítorí mẹ́rin, mi ò ní yí ọwọ́ mi pa dà,
Nítorí wọ́n kó gbogbo àwọn èèyàn nígbèkùn,+ wọ́n sì fà wọ́n lé Édómù lọ́wọ́.
7 Torí náà, màá rán iná sí ògiri Gásà,+
Á sì jó àwọn ilé gogoro rẹ̀ tó láàbò run.
8 Màá pa àwọn tó ń gbé Áṣídódì run,+
Àti àwọn tó ń ṣàkóso* ní Áṣíkẹ́lónì;+
Màá fìyà jẹ Ẹ́kírónì,+
Àwọn Filísínì tó ṣẹ́ kù yóò sì ṣègbé,”+ ni Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí.’
9 Ohun tí Jèhófà sọ nìyí,
‘Nítorí ìdìtẹ̀ mẹ́ta Tírè+ àti nítorí mẹ́rin, mi ò ní yí ọwọ́ mi pa dà,
Nítorí wọ́n kó gbogbo àwọn tí wọ́n mú nígbèkùn, wọ́n sì fà wọ́n lé Édómù lọ́wọ́,
Àti nítorí pé wọn kò rántí májẹ̀mú àwọn arákùnrin.+
10 Torí náà, màá rán iná sí ògiri Tírè,
Á sì jó àwọn ilé gogoro rẹ̀ tó láàbò run.’+
11 Ohun tí Jèhófà sọ nìyí,
‘Nítorí ìdìtẹ̀ mẹ́ta Édómù+ àti nítorí mẹ́rin, mi ò ní yí ọwọ́ mi pa dà,
Nítorí ó fi idà lépa arákùnrin rẹ̀,+
Àti nítorí pé ó kọ̀ láti ṣàánú rẹ̀;
Ó ń fi ìbínú rẹ̀ fà wọ́n ya láìdáwọ́ dúró,
Kò sì yéé bínú sí wọn.+
13 Ohun tí Jèhófà sọ nìyí,
‘“Nítorí ìdìtẹ̀ mẹ́ta àwọn ọmọ Ámónì+ àti nítorí mẹ́rin, mi ò ní yí ọwọ́ mi pa dà,
Nítorí wọ́n la inú àwọn aboyún Gílíádì kí wọ́n lè mú agbègbè tiwọn fẹ̀ sí i.+
14 Torí náà, màá sọ iná sí ògiri Rábà,+
Á sì jó àwọn ilé gogoro rẹ̀ tó láàbò run,
Ariwo á sọ ní ọjọ́ ogun,
Àti ìjì líle ní ọjọ́ ẹ̀fúùfù.
15 Ọba wọn á sì lọ sí ìgbèkùn pẹ̀lú àwọn ìjòyè rẹ̀,”+ ni Jèhófà wí.’
2 “Ohun tí Jèhófà sọ nìyí,
‘“Nítorí ìdìtẹ̀* mẹ́ta Móábù+ àti nítorí mẹ́rin, mi ò ní yí ọwọ́ mi pa dà,
Nítorí pé ó jó egungun ọba Édómù láti fi ṣe ẹfun.
2 Torí náà, màá rán iná sí Móábù,
Á sì jó àwọn ilé gogoro tó láàbò ti Kíríọ́tì+ run;
Móábù á kú sínú ariwo,
Nígbà tí ariwo bá sọ nítorí ogun, tí ìró ìwo sì dún.+
3 Màá mú alákòóso* kúrò ní àárín Móábù
Màá sì pa gbogbo àwọn ìjòyè rẹ̀ pẹ̀lú alákòóso rẹ̀,”+ ni Jèhófà wí.’
4 Ohun tí Jèhófà sọ nìyí,
‘Nítorí ìdìtẹ̀ mẹ́ta Júdà+ àti nítorí mẹ́rin, mi ò ní yí ọwọ́ mi pa dà,
Nítorí pé wọn kò tẹ̀ lé òfin* Jèhófà
Àti nítorí pé wọn kò pa àwọn ìlànà rẹ̀ mọ́;+
Irọ́ tí àwọn baba ńlá wọn tọ̀ lẹ́yìn ti mú kí wọ́n ṣìnà.+
6 Ohun tí Jèhófà sọ nìyí,
‘Nítorí ìdìtẹ̀ mẹ́ta Ísírẹ́lì+ àti nítorí mẹ́rin, mi ò ní yí ọwọ́ mi pa dà,
Torí wọ́n ta olódodo nítorí fàdákà
Àti tálákà nítorí iye owó bàtà ẹsẹ̀ méjì.+
Ọkùnrin kan àti bàbá rẹ̀ bá ọmọbìnrin kan náà ní àṣepọ̀,
Wọ́n sì ń sọ orúkọ mímọ́ mi di aláìmọ́.
8 Orí àwọn ẹ̀wù tí wọ́n gbà láti fi ṣe ìdúró*+ ni wọ́n ń sùn gbalaja sí lẹ́gbẹ̀ẹ́ gbogbo pẹpẹ;+
Owó ìtanràn tí wọ́n gbà ni wọ́n fi ra wáìnì tí wọ́n ń mu ní ilé* àwọn ọlọ́run wọn.’
9 ‘Ṣùgbọ́n èmi ni mo pa Ámórì rẹ́ ní ìṣojú wọn,+
Ẹni tó ga bí igi kédárì, tó sì ní agbára bí àwọn igi ràgàjì;*
Mo pa èso rẹ̀ run lókè àti gbòǹgbò rẹ̀ nísàlẹ̀.+
10 Mo mú yín kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì,+
Ogójì (40) ọdún ni mo fi mú yín la aginjù já,+
Kí ẹ lè gba ilẹ̀ Ámórì.
11 Mo yan àwọn kan lára àwọn ọmọkùnrin yín láti jẹ́ wòlíì+
Àti lára àwọn ọ̀dọ́kùnrin yín láti jẹ́ Násírì.+
Àbí bẹ́ẹ̀ kọ́, ẹ̀yin ọmọ Ísírẹ́lì?’ ni Jèhófà wí.
13 Nítorí náà, màá tẹ̀ yín rẹ́ ní ibùgbé yín,
Bíi kẹ̀kẹ́ tó kó ọkà gígé ṣe ń tẹ ohun tó wà lábẹ́ rẹ̀ ní àtẹ̀rẹ́.
14 Asáré tete kò ní rí ibi sá sí,+
Alágbára kò ní lókun mọ́,
Kò sì ní sí jagunjagun tó máa lè gba ẹ̀mí* ara rẹ̀ là.
15 Tafàtafà kò ní lè dúró,
Asáré tete kò ní lè sá àsálà,
Bẹ́ẹ̀ ni agẹṣin kò ní lè gba ẹ̀mí* ara rẹ̀ là.
3 “Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ tí Jèhófà sọ nípa yín, ẹ̀yin ọmọ Ísírẹ́lì, nípa gbogbo ìdílé tí mo mú jáde kúrò nílẹ̀ Íjíbítì:
2 ‘Ẹ̀yin nìkan ni mo mọ̀ nínú gbogbo ìdílé tó wà láyé.+
Ìdí nìyẹn tí màá fi mú kí ẹ jíhìn nítorí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ yín.+
3 Ǹjẹ́ àwọn méjì lè jọ rìn láìjẹ́ pé wọ́n ṣe àdéhùn?*
4 Ǹjẹ́ kìnnìún máa ké ramúramù nínú igbó láìjẹ́ pé ó ti rí ẹran tó fẹ́ pa?
Ǹjẹ́ ọmọ kìnnìún* máa kùn hùn-ùn láti ibi tó fara pa mọ́ sí láìjẹ́ pé ọwọ́ rẹ̀ ti tẹ nǹkan kan?
5 Ǹjẹ́ ẹyẹ lè kó sí pańpẹ́ lórí ilẹ̀ láìjẹ́ pé ẹnì kan ti dẹ pańpẹ́ náà?*
Ṣé pańpẹ́ lè ré lórí ilẹ̀ nígbà tí kò tíì mú nǹkan kan?
6 Tí èèyàn bá fun ìwo nínú ìlú, ǹjẹ́ àyà àwọn ará ìlú kò ní já?
Tí àjálù bá ṣẹlẹ̀ nínú ìlú, ǹjẹ́ kì í ṣe Jèhófà ló fà á?
7 Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ kò ní ṣe ohunkóhun
Láìjẹ́ pé ó ti fi àṣírí ọ̀rọ̀ náà* han àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ tó jẹ́ wòlíì.+
8 Kìnnìún ti ké ramúramù!+ Ta ni kò ní bẹ̀rù?
Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ ti sọ̀rọ̀! Ta ni kò ní sọ tẹ́lẹ̀?’+
9 ‘Ẹ kéde rẹ̀ lórí àwọn ilé gogoro tó láàbò ní Áṣídódì
Àti lórí àwọn ilé gogoro tó láàbò nílẹ̀ Íjíbítì.
Ẹ sọ pé: “Ẹ kóra jọ sórí àwọn òkè Samáríà;+
Ẹ wo ìdàrúdàpọ̀ tó wà ní àárín rẹ̀
Àti jìbìtì tó wà nínú rẹ̀.+
10 Nítorí wọn kò mọ bí a ti ń ṣe ohun tí ó tọ́,” ni Jèhófà wí,
“Àwọn tó ń mú ìwà ipá àti ìparun pọ̀ sí i nínú àwọn ilé gogoro wọn tó láàbò.”’
11 Nítorí náà, ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí,
‘Ọ̀tá kan máa yí ilẹ̀ náà ká,+
Á sì mú kí agbára rẹ tán,
Ohun tó wà nínú àwọn ilé gogoro rẹ tó láàbò ni wọ́n á sì kó lọ.’+
12 Ohun tí Jèhófà sọ nìyí,
‘Bí olùṣọ́ àgùntàn ṣe ń já ẹsẹ̀ méjì tàbí etí kan gbà kúrò lẹ́nu kìnnìún,
Bẹ́ẹ̀ ni a ó ṣe já àwọn ọmọ Ísírẹ́lì gbà,
Àwọn tó ń jókòó sórí ibùsùn rèǹtèrente àti sórí àga ìnàyìn tó rẹwà* ní Samáríà.’+
13 ‘Ẹ gbọ́, kí ẹ sì kìlọ̀ fún* ilé Jékọ́bù,’ ni Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ, Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun wí.
14 ‘Ní ọjọ́ tí màá mú kí Ísírẹ́lì jíhìn nítorí ìdìtẹ̀* rẹ̀,+
Ni màá mú kí àwọn pẹpẹ Bẹ́tẹ́lì pẹ̀lú jíhìn;+
A ó ṣẹ́ àwọn ìwo pẹpẹ náà, wọ́n á sì já bọ́ sílẹ̀.+
15 Màá wó ilé ìgbà òtútù àti ilé ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn lulẹ̀.’
4 “Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ yìí, ẹ̀yin abo màlúù Báṣánì,
Tó wà lórí òkè Samáríà,+
Ẹ̀yin obìnrin tó ń lu àwọn aláìní ní jìbìtì,+ tó sì ń ni àwọn tálákà lára,
Tó ń sọ fún àwọn ọkọ* wọn pé, ‘Ẹ gbé ọtí wá ká mu!’
2 Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ ti fi ìjẹ́mímọ́ rẹ̀ búra pé,
‘“Wò ó! Ọjọ́ ń bọ̀ nígbà tó máa fi ìkọ́ alápatà gbé yín sókè
Tí á sì fi ìwọ̀ ẹja gbé àwọn tó ṣẹ́ kù lára yín.
3 Kálukú yín máa gba àlàfo ara ògiri tó wà níwájú rẹ̀ jáde lọ;
A ó sì lé yín sí Hámọ́nì,” ni Jèhófà wí.’
5 Ẹ fi búrẹ́dì tó ní ìwúkàrà rú ẹbọ ìdúpẹ́;+
Ẹ sì kéde àwọn ọrẹ àtinúwá yín!
Nítorí ohun tí ẹ fẹ́ nìyẹn, ẹ̀yin ọmọ Ísírẹ́lì,’ ni Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí.
6 ‘Ní tèmi, mo mú kí eyín yín mọ́ nítorí àìsí oúnjẹ* ní gbogbo àwọn ìlú yín
Mi ò sì jẹ́ kí oúnjẹ wà ní gbogbo ilé yín;+
Síbẹ̀, ẹ kò pa dà sọ́dọ̀ mi,’+ ni Jèhófà wí.
7 ‘Mo tún fawọ́ òjò sẹ́yìn kúrò lọ́dọ̀ yín nígbà tí ìkórè ṣì ku oṣù mẹ́ta;+
Mo mú kí òjò rọ̀ sí ìlú kan àmọ́ mi ò jẹ́ kó rọ̀ sí ìlú míì.
Òjò máa rọ̀ sí ilẹ̀ kan,
Àmọ́ ilẹ̀ tí òjò kò rọ̀ sí máa gbẹ.
8 Àwọn èèyàn ìlú méjì tàbí mẹ́ta ń rọ́ lọ sí ìlú kan ṣoṣo kí wọ́n lè mu omi,+
Àmọ́ kò tẹ́ wọn lọ́rùn;
Síbẹ̀, ẹ kò pa dà sọ́dọ̀ mi,’+ ni Jèhófà wí.
9 ‘Mo fi ooru tó ń jóni àti èbíbu* kọ lù yín.+
Ẹ̀ ń mú kí àwọn ọgbà yín àti oko àjàrà yín di púpọ̀,+
Ṣùgbọ́n eéṣú ló jẹ igi ọ̀pọ̀tọ́ yín àti igi ólífì yín run;
Síbẹ̀, ẹ kò pa dà sọ́dọ̀ mi,’+ ni Jèhófà wí.
10 ‘Mo rán àjàkálẹ̀ àrùn sáàárín yín bíi ti Íjíbítì.+
Mo fi idà pa àwọn ọ̀dọ́kùnrin yín,+ mo sì gba àwọn ẹṣin yín.+
Mo mú kí òórùn àwọn tó kú ní ibùdó yín gba afẹ́fẹ́ kan;+
Síbẹ̀, ẹ kò pa dà sọ́dọ̀ mi,’ ni Jèhófà wí.
11 ‘Mo pa ilẹ̀ yín run
Bí Ọlọ́run ṣe pa Sódómù àti Gòmórà run.+
Ẹ sì dà bí igi tí a fà yọ kúrò nínú iná;
Síbẹ̀, ẹ kò pa dà sọ́dọ̀ mi,’+ ni Jèhófà wí.
12 Torí náà, màá tún fìyà jẹ ọ́, ìwọ Ísírẹ́lì.
Nítorí ohun tí màá ṣe sí ọ yìí,
Múra sílẹ̀ láti pàdé Ọlọ́run rẹ, ìwọ Ísírẹ́lì.
13 Nítorí, wò ó! Òun ló dá àwọn òkè+ àti afẹ́fẹ́;+
Ó ń sọ èrò Rẹ̀ fún àwọn èèyàn,
Ó ń sọ ìmọ́lẹ̀ di òkùnkùn,+
Ó ń rìn lórí àwọn ibi gíga ayé;+
Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun ni orúkọ rẹ̀.”
5 “Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ yìí tí màá fi orin arò* sọ fún yín, ilé Ísírẹ́lì:
2 ‘Wúńdíá náà, Ísírẹ́lì, ti ṣubú;
Kò lè dìde mọ́.
Wọ́n ti pa á tì sórí ilẹ̀ rẹ̀;
Kò sí ẹnì kankan tó máa gbé e dìde.’
3 “Ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí:
‘Ìlú tó ń jáde lọ sí ogun pẹ̀lú ẹgbẹ̀rún (1,000) máa ṣẹ́ ku ọgọ́rùn-ún (100);
Èyí tó sì ń jáde lọ pẹ̀lú ọgọ́rùn-ún (100) máa ṣẹ́ ku mẹ́wàá fún ilé Ísírẹ́lì.’+
4 “Ohun tí Jèhófà sọ fún ilé Ísírẹ́lì nìyí:
‘Wá mi, kí o lè máa wà láàyè.+
Ẹ má lọ sí Gílígálì,+ ẹ má sì kọjá sí Bíá-ṣébà,+
Torí ó dájú pé Gílígálì máa lọ sí ìgbèkùn,+
Bẹ́tẹ́lì á sì di asán.*
6 Wá Jèhófà, kí o lè máa wà láàyè,+
Kó má bàa bú jáde bí iná sórí ilé Jósẹ́fù,
Kó má bàa jó Bẹ́tẹ́lì run láìsí ẹni tó máa pa iná náà.
8 Ẹni tó dá àgbájọ ìràwọ̀ Kímà* àti àgbájọ ìràwọ̀ Késílì,*+
Ẹni tó ń sọ òkùnkùn biribiri di ìmọ́lẹ̀ òwúrọ̀,
Ẹni tó ń mú kí ọ̀sán ṣókùnkùn bí òru,+
Ẹni tó ń wọ́ omi jọ látinú òkun
Kí ó lè dà á sórí ilẹ̀,+
Jèhófà ni orúkọ rẹ̀.
9 Á mú kí ìparun dé bá alágbára lójijì,
Á sì mú kí àwọn ibi olódi pa run.
10 Wọ́n kórìíra àwọn tó ń báni wí ní ẹnubodè ìlú,
Wọ́n sì kórìíra àwọn tó ń sọ òtítọ́.+
11 Nítorí pé ẹ̀ ń gba owó oko* lọ́wọ́ àwọn aláìní tí ẹ gbé oko fún
Ẹ sì ń gba ọkà lọ́wọ́ wọn bí ìṣákọ́lẹ̀,*+
Ẹ kò ní máa gbé inú àwọn ilé tí ẹ fi òkúta gbígbẹ́ kọ́+
Bẹ́ẹ̀ ni ẹ kò ní máa mu wáìnì àwọn ọgbà àjàrà dáradára tí ẹ gbìn.+
12 Nítorí mo mọ bí ìdìtẹ̀* yín ṣe pọ̀ tó
Àti bí ẹ̀ṣẹ̀ yín ṣe pọ̀ tó
Ẹ̀ ń dààmú àwọn olódodo,
Ẹ̀ ń gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀,*
Ẹ sì ń fi ẹ̀tọ́ àwọn aláìní dù wọ́n ní ẹnubodè.+
13 Torí náà, àwọn tó ní ìjìnlẹ̀ òye máa dákẹ́ jẹ́ẹ́ ní àkókò yẹn,
Nítorí ó máa jẹ́ àkókò àjálù.+
Nígbà náà, Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun á lè wà pẹ̀lú yín,
Bí ẹ ti sọ pé ó wà pẹ̀lú yín.+
Bóyá Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun
Máa fi ojúure hàn sí àwọn tó ṣẹ́ kù lára Jósẹ́fù.’+
16 “Nítorí náà, ohun tí Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun, àní Jèhófà sọ nìyí:
‘Ìpohùnréré ẹkún máa wà ní gbogbo ojúde ìlú,
Àti ní gbogbo ojú ọ̀nà, àwọn èèyàn á máa sọ pé, “Áà, ó mà ṣe o!”
Wọ́n á pe àwọn àgbẹ̀ pé kí wọ́n wá ṣọ̀fọ̀
Àti àwọn tó ń fi ẹkún sísun ṣiṣẹ́ ṣe láti pohùn réré ẹkún.’
17 ‘Ìpohùnréré ẹkún máa wà ní gbogbo ọgbà àjàrà;+
Nítorí màá la àárín rẹ kọjá,’ ni Jèhófà wí.
18 ‘Ẹ̀yin tí ẹ̀ ń fẹ́ kí ọjọ́ Jèhófà dé, ẹ gbé!+
Àǹfààní wo wá ni ọjọ́ Jèhófà máa ṣe yín?+
Òkùnkùn ló máa jẹ́, kì í ṣe ìmọ́lẹ̀.+
19 Ńṣe ló máa dà bí ọkùnrin kan tó ń sá fún kìnnìún, tó wá pàdé bíárì,
Nígbà tó wọ ilé rẹ̀, tó fi ọwọ́ ti ògiri, ejò bù ú ṣán.
20 Ọjọ́ Jèhófà máa jẹ́ òkùnkùn, kì í ṣe ìmọ́lẹ̀;
Ó máa jẹ́ ìṣúdùdù, kì í ṣe ìtànyòò.
22 Kódà bí ẹ tiẹ̀ rú odindi ẹbọ sísun, tí ẹ sì fún mi ní ẹ̀bùn,
Inú mi ò ní dùn sí ọrẹ wọ̀nyẹn;+
Mi ò sì ní fi ojúure wo àwọn ẹbọ ìrẹ́pọ̀ tí ẹ fi ẹran àbọ́sanra rú.+
23 Gbé ariwo orin rẹ kúrò lọ́dọ̀ mi;
Má sì jẹ́ kí n gbọ́ ìró ohun ìkọrin olókùn tín-ín-rín rẹ.+
24 Jẹ́ kí ìdájọ́ òdodo ṣàn wálẹ̀ bí omi,+
Àti òdodo bí odò tó ń ṣàn nígbà gbogbo.
25 Ǹjẹ́ ẹ mú ẹbọ àti ọrẹ wá fún mi
Ní gbogbo ogójì (40) ọdún tí ẹ fi wà ní aginjù, ilé Ísírẹ́lì?+
26 Ní báyìí, ẹ ó gbé Sákútì ọba yín àti Káíwánì kúrò,*
Àwọn ère yín, ìràwọ̀ ọlọ́run yín, tí ẹ ṣe fún ara yín,
27 Màá sì rán yín lọ sí ìgbèkùn ní ìkọjá Damásíkù,’+ ni ẹni tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun wí.”+
6 “Àwọn tó dá ara wọn lójú* ní Síónì gbé!
Àwọn tí ọkàn wọn balẹ̀ lórí òkè Samáríà,+
Àwọn olókìkí èèyàn nínú àwọn orílẹ̀-èdè tó gba iwájú,
Àwọn tí ilé Ísírẹ́lì ń lọ sọ́dọ̀ wọn!
2 Ẹ ré kọjá sí Kálínè, kí ẹ sì wò.
Ẹ ti ibẹ̀ lọ sí Hámátì Ńlá,+
Kí ẹ sì lọ sí Gátì ti àwọn Filísínì.
Ṣé wọ́n sàn ju àwọn ìjọba yìí,*
Tàbí ṣé ilẹ̀ wọn tóbi ju tiyín lọ ni?
4 Wọ́n ń dùbúlẹ̀ sórí àwọn ibùsùn tí wọ́n fi eyín erin ṣe,+ wọ́n sì ń nà gbalaja sórí àga tìmùtìmù,+
Wọ́n ń jẹ àwọn àgbò inú agbo ẹran àti àwọn ọmọ màlúù* tí wọ́n bọ́ sanra;+
5 Wọ́n ń kọ orin sí ìró háàpù,*+
Bíi Dáfídì, wọ́n ṣe àwọn ohun èlò ìkọrin;+
Wọ́n sì ń fi òróró tó dára jù lọ para.
Àmọ́ àjálù tó dé bá Jósẹ́fù kò dùn wọ́n.*+
7 Nítorí náà, àwọn ló máa kọ́kọ́ lọ sí ìgbèkùn,+
Àríyá aláriwo àwọn tó nà gbalaja sì máa dópin.
8 ‘Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ ti fi ara* rẹ̀ búra,’+ àní Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun sọ pé,
‘“Mo kórìíra ìgbéraga Jékọ́bù,+
Mo sì kórìíra àwọn ilé gogoro rẹ̀ tó láàbò,+
Màá sì fa ìlú náà àti ohun tó wà nínú rẹ̀ lé àwọn ọ̀tá lọ́wọ́.+
9 “‘“Bí ó bá sì ṣẹ́ ku ọkùnrin mẹ́wàá sínú ilé kan, àwọn náà máa kú. 10 Mọ̀lẹ́bí* kan á wá gbé wọn jáde, á sì sun wọ́n lọ́kọ̀ọ̀kan. Á kó egungun wọn jáde kúrò nínú ilé; á sì béèrè lọ́wọ́ ẹni tó bá wà ní àwọn yàrá inú pé, ‘Ṣé wọ́n ṣì kù lọ́dọ̀ rẹ?’ Ẹni náà á fèsì pé, ‘Kò sí ẹnì kankan!’ Nígbà náà, á sọ pé, ‘Dákẹ́! Nítorí kì í ṣe àkókò yìí ló yẹ ká máa pe Jèhófà.’”
12 Ǹjẹ́ àwọn ẹṣin máa ń sáré lórí àpáta,
Àbí ẹnikẹ́ni lè fi màlúù túlẹ̀ lórí rẹ̀?
13 Ẹ̀ ń yọ̀ lórí nǹkan tí kò ní láárí,
Ẹ sì ń sọ pé, “Ǹjẹ́ kì í ṣe okun wa ló mú ká di alágbára?”*+
14 Nítorí náà, ẹ̀yin èèyàn ilé Ísírẹ́lì, màá gbé orílẹ̀-èdè kan dìde sí yín’+ ni Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun wí,
‘Wọ́n á sì ni yín lára láti Lebo-hámátì*+ títí dé Àfonífojì Árábà.’”
7 Ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ fi hàn mí nìyí: Wò ó! Ó kó ọ̀wọ́ eéṣú jọ ní ìgbà tí irúgbìn àgbìnkẹ́yìn* bẹ̀rẹ̀ sí í dàgbà. Èyí ni irúgbìn àgbìnkẹ́yìn lẹ́yìn tí wọ́n ti gé koríko ọba. 2 Nígbà tí àwọn eéṣú náà jẹ ohun ọ̀gbìn ilẹ̀ náà tán, mo sọ pé: “Áà, Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ, jọ̀wọ́, dárí jì wọ́n!+ Jékọ́bù kò ní okun!+ Báwo ló ṣe máa là á já?”*
3 Nítorí náà, Jèhófà pa èrò rẹ̀ dà.*+ “Kò ní ṣẹlẹ̀,” ni Jèhófà wí.
4 Ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ fi hàn mí nìyí: Wò ó! Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ lo iná láti fìyà jẹ àwọn èèyàn rẹ̀. Iná náà lá alagbalúgbú omi gbẹ, ó sì jẹ apá kan ilẹ̀ náà run. 5 Mo sì sọ pé: “Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ, jọ̀wọ́, má ṣe bẹ́ẹ̀.+ Jékọ́bù kò ní okun!+ Báwo ló ṣe máa là á já?”*
6 Nítorí náà, Jèhófà pa èrò rẹ̀ dà.*+ “Èyí náà kò ní ṣẹlẹ̀,” ni Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí.
7 Ohun tó fi hàn mí nìyí: Wò ó! Jèhófà dúró lórí ògiri kan tí wọ́n fi okùn ìwọ̀n mú tọ́ nígbà tí wọ́n kọ́ ọ, okùn ìwọ̀n kan sì wà ní ọwọ́ rẹ̀. 8 Ìgbà náà ni Jèhófà sọ fún mi pé: “Kí lo rí, Émọ́sì?” Torí náà, mo sọ pé: “Okùn ìwọ̀n.” Jèhófà sì sọ pé: “Wò ó, màá fi okùn ìwọ̀n wọn àwọn èèyàn mi Ísírẹ́lì. Mi ò sì ní forí jì wọ́n mọ́.+ 9 Àwọn ibi gíga Ísákì+ máa di ahoro, àwọn ibùjọsìn Ísírẹ́lì á sì pa run;+ màá fi idà kọ lu ilé Jèróbóámù.”+
10 Amasááyà àlùfáà Bẹ́tẹ́lì+ ránṣẹ́ sí Jèróbóámù+ ọba Ísírẹ́lì pé: “Émọ́sì ń dìtẹ̀ sí ọ láàárín ilé Ísírẹ́lì.+ Àwọn èèyàn ilẹ̀ náà kò lè rí ara gba gbogbo ọ̀rọ̀ rẹ̀.+ 11 Nítorí ohun tí Émọ́sì sọ nìyí, ‘Idà ni yóò pa Jèróbóámù, ó sì dájú pé Ísírẹ́lì máa lọ sí ìgbèkùn láti ilẹ̀ rẹ̀.’”+
12 Ìgbà náà ni Amasááyà sọ fún Émọ́sì pé: “Ìwọ aríran, máa lọ, sá lọ sí ilẹ̀ Júdà, ibẹ̀ ni kí o ti máa wá bí wàá ṣe jẹun,* ibẹ̀ sì ni o ti lè sọ tẹ́lẹ̀.+ 13 Ṣùgbọ́n ìwọ kò gbọ́dọ̀ sọ tẹ́lẹ̀ ní Bẹ́tẹ́lì mọ́,+ nítorí pé ibùjọsìn ọba ni,+ ilé ìjọba sì ni.”
14 Ìgbà náà ni Émọ́sì dá Amasááyà lóhùn pé: “Wòlíì kọ́ ni mí tẹ́lẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni èmi kì í ṣe ọmọ wòlíì; olùṣọ́ agbo ẹran ni mí,+ mo sì máa ń tọ́jú igi ọ̀pọ̀tọ́ síkámórè.* 15 Àmọ́ Jèhófà sọ fún mi pé kí n má ṣe da agbo ẹran mọ́, Jèhófà sì sọ fún mi pé, ‘Lọ, sọ tẹ́lẹ̀ fún àwọn èèyàn mi Ísírẹ́lì.’+ 16 Torí náà, gbọ́ ọ̀rọ̀ Jèhófà: ‘Ìwọ ń sọ pé, “Ìwọ kò gbọ́dọ̀ sọ tẹ́lẹ̀ lòdì sí Ísírẹ́lì,+ ìwọ kò sì gbọ́dọ̀ kéde ìkìlọ̀+ fún ilé Ísákì.” 17 Nítorí náà, ohun tí Jèhófà sọ nìyí: “Aya rẹ máa di aṣẹ́wó ní ìlú yìí, idà ni yóò pa àwọn ọmọkùnrin rẹ àti àwọn ọmọbìnrin rẹ. Okùn ìdíwọ̀n ni wọ́n á fi pín ilẹ̀ rẹ, orí ilẹ̀ àìmọ́ ni wàá sì kú sí; ó sì dájú pé Ísírẹ́lì máa lọ sí ìgbèkùn láti ilẹ̀ rẹ̀.”’”+
8 Ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ fi hàn mí nìyí: Wò ó! Apẹ̀rẹ̀ kan tí èso ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn wà nínú rẹ̀. 2 Ó wá sọ pé, “Kí lo rí, Émọ́sì?” Mo fèsì pé, “Apẹ̀rẹ̀ tí èso ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn wà nínú rẹ̀.” Jèhófà wá sọ fún mi pé: “Òpin ti dé bá àwọn èèyàn mi Ísírẹ́lì. Èmi kò ní forí jì wọ́n mọ́.+ 3 ‘Àwọn orin tẹ́ńpìlì máa di igbe ẹkún ní ọjọ́ yẹn,’+ ni Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí. ‘Òkú á sì sùn lọ bẹẹrẹ níbi gbogbo.+ Dákẹ́!’
4 Ẹ gbọ́ èyí, ẹ̀yin tí ẹ̀ ń ni àwọn tálákà lára
Tí ẹ sì ń pa àwọn oníwà pẹ̀lẹ́ ilẹ̀ yìí,+
5 Ẹ̀yin tí ẹ̀ ń sọ pé, ‘Ìgbà wo ni àjọ̀dún òṣùpá tuntun máa parí,+ ká lè ta àwọn hóró ọkà wa,
Àti ìparí Sábáàtì,+ ká lè gbé hóró ọkà lọ fún títà?
Ká lè sọ òṣùwọ̀n eéfà* di kékeré
Kí a sì sọ ṣékélì* di ńlá,
Kí a dọ́gbọ́n sí àwọn òṣùwọ̀n wa, kí a lè fi tanni jẹ;+
6 Kí a lè fi fàdákà ra àwọn aláìní
Kí a sì fi owó bàtà ẹsẹ̀ méjì ra àwọn tálákà,+
Kí a sì lè ta èyí tí kò dáa lára ọkà.’
Ǹjẹ́ kò ní ru sókè bí odò Náílì,
Kí ó sì bì síwá sẹ́yìn, kí ó wá rọlẹ̀ bí odò Náílì Íjíbítì?’+
9 ‘Ní ọjọ́ yẹn,’ ni Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí,
‘Màá mú kí oòrùn wọ̀ ní ọ̀sán gangan,
Màá sì mú kí ilẹ̀ náà ṣókùnkùn ní ojúmọmọ.+
Màá sán aṣọ ọ̀fọ̀* mọ́ gbogbo ìbàdí, màá sì mú gbogbo orí pá;
Màá ṣe é bí ìgbà téèyàn ń ṣọ̀fọ̀ nítorí ọmọkùnrin rẹ̀ kan ṣoṣo,
Màá sì mú kí ìgbẹ̀yìn rẹ̀ dà bí ọjọ́ tó korò.’
11 ‘Wò ó! Ọjọ́ ń bọ̀,’ ni Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí,
‘Nígbà tí màá rán ìyàn sí ilẹ̀ náà,
Kì í ṣe ìyàn oúnjẹ tàbí ti omi,
Bí kò ṣe ti gbígbọ́ ọ̀rọ̀ Jèhófà.+
12 Wọ́n á ta gọ̀ọ́gọ̀ọ́ láti òkun dé òkun
Láti àríwá sí ìlà oòrùn.*
Wọ́n á máa wá ọ̀rọ̀ Jèhófà káàkiri, ṣùgbọ́n wọn ò ní rí i.
13 Ní ọjọ́ yẹn, àwọn arẹwà wúńdíá máa dá kú,
Àti àwọn ọ̀dọ́kùnrin pàápàá, nítorí òùngbẹ náà;
14 Àwọn tó ń fi ẹ̀ṣẹ̀ Samáríà+ búra, tí wọ́n sì ń sọ pé,
“Bí ọlọ́run rẹ ti wà láàyè, ìwọ Dánì!”+
Àti “Bí ọ̀nà Bíá-ṣébà+ ti ń bẹ!”
Wọ́n á ṣubú, wọn ò sì ní dìde mọ́.’”+
9 Mo rí i tí Jèhófà+ dúró lókè pẹpẹ, ó sì sọ pé: “Lu orí òpó, àwọn ibi àbáwọlé á sì mì jìgìjìgì. Gé orí wọn kúrò, màá sì fi idà pa èyí tó gbẹ̀yìn lára wọn. Kò sí ẹnì kankan lára wọn tó máa lè sá lọ tàbí tó máa sá àsálà.+
2 Bí wọ́n bá walẹ̀ lọ sínú Isà Òkú,*
Ibẹ̀ ni ọwọ́ mi á ti tẹ̀ wọ́n;
Bí wọ́n bá sì gòkè lọ sí ọ̀run,
Ibẹ̀ ni màá ti fà wọ́n sọ̀ kalẹ̀.
3 Bí wọ́n bá fara pa mọ́ sórí òkè Kámẹ́lì,
Ibẹ̀ ni màá ti wá wọn kàn, màá sì mú wọn.+
Bí wọ́n bá sì fara pa mọ́ kúrò ní ojú mi ní ìsàlẹ̀ òkun,
Ibẹ̀ ni màá ti pàṣẹ fún ejò, á sì bù wọ́n ṣán.
4 Bí àwọn ọ̀tá bá kó wọn lọ sí oko ẹrú,
Ibẹ̀ ni màá ti pàṣẹ fún idà, yóò sì pa wọ́n;+
Màá dájú sọ wọ́n, kì í ṣe fún ire, bí kò ṣe fún ibi.+
5 Nítorí Olúwa Ọba Aláṣẹ, Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun, ni Ẹni tó fọwọ́ kan ilẹ̀ náà,*
Kí ó lè yọ́,+ kí gbogbo àwọn tó ń gbé lórí rẹ̀ sì ṣọ̀fọ̀;+
Gbogbo rẹ̀ á ru sókè bí odò Náílì,
Á sì rọlẹ̀ bí odò Náílì Íjíbítì.+
6 ‘Ẹni tó ṣe àwọn àtẹ̀gùn Rẹ̀ lọ sí ọ̀run,
Tó sì dá àwọn nǹkan sí òkè ayé;
Ẹni tó ń wọ́ omi jọ látinú òkun,
Kí ó lè dà á sórí ilẹ̀,+
Jèhófà ni orúkọ rẹ̀.’+
7 ‘Ǹjẹ́ kì í ṣe bí àwọn ọmọ Kúṣì lẹ jẹ́ sí mi, ẹ̀yin ọmọ Ísírẹ́lì?’ ni Jèhófà wí.
‘Ṣé mi ò mú Ísírẹ́lì jáde kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì+
8 ‘Wò ó! Ojú Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wà lára ìjọba tó ń dẹ́ṣẹ̀,
Á sì pa á rẹ́ kúrò lórí ilẹ̀.+
Ṣùgbọ́n, mi ò ní pa gbogbo ilé Jékọ́bù rẹ́,’+ ni Jèhófà wí.
9 ‘Wò ó! Mò ń pàṣẹ,
Màá mi ilé Ísírẹ́lì jìgìjìgì láàárín gbogbo orílẹ̀-èdè,+
Bí èèyàn ṣe ń mi ajọ̀ jìgìjìgì,
Tí òkúta róbótó kankan kò sì ní bọ́ sílẹ̀.
10 Idà ni yóò pa gbogbo àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ tó wà nínú àwọn èèyàn mi,
Àwọn tó ń sọ pé, “Àjálù kò ní sún mọ́ wa tàbí kó dé ọ̀dọ̀ wa.”’
11 ‘Ní ọjọ́ yẹn, màá gbé àtíbàbà* Dáfídì+ tó ti wó dìde,
Màá sì tún àwọn àlàfo rẹ̀* ṣe,
Màá tún àwókù rẹ̀ kọ́;
Màá tún un kọ́, á sì rí bíi ti tẹ́lẹ̀,+
12 Kí wọ́n lè gba ohun tó ṣẹ́ kù nínú Édómù,+
Àti ohun tó ṣẹ́ kù nínú gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè tí a fi orúkọ mi pè,’ ni Jèhófà, ẹni tó ń ṣe nǹkan yìí wí.
13 ‘Wò ó! Ọjọ́ ń bọ̀,’ ni Jèhófà wí,
‘Nígbà tí atúlẹ̀ máa lé olùkórè bá,
Tí ẹni tó ń fẹsẹ̀ tẹ èso àjàrà á sì lé ẹni tó gbé irúgbìn bá;+
Tí wáìnì dídùn á máa kán tótó láti ara àwọn òkè ńlá,+
14 Màá kó àwọn èèyàn mi Ísírẹ́lì tó wà ní ìgbèkùn pa dà,+
Wọ́n á tún àwọn ìlú tó ti di ahoro kọ́, wọ́n á sì máa gbé inú wọn;+
Wọ́n á gbin ọgbà àjàrà, wọ́n á sì mu wáìnì wọn,+
Wọ́n á ṣe ọgbà, wọ́n á sì jẹ èso wọn.’+
15 ‘Màá gbìn wọ́n sórí ilẹ̀ wọn,
A kò sì ní fà wọ́n tu mọ́
Kúrò lórí ilẹ̀ tí mo fún wọn,’+ ni Jèhófà Ọlọ́run rẹ wí.”
Ó túmọ̀ sí “Ẹrù” tàbí “Gbé Ẹrù.”
Tàbí “ìwà ọ̀daràn.”
Ní Héb., “àwọn tó ń di ọ̀pá àṣẹ mú.”
Ní Héb., “àwọn tó ń di ọ̀pá àṣẹ mú.”
Tàbí “ìwà ọ̀daràn.”
Ní Héb., “onídàájọ́.”
Tàbí “ìtọ́ni.”
Tàbí “ìdógò.”
Tàbí “tẹ́ńpìlì.”
Tàbí “igi óákù.”
Tàbí “ọkàn.”
Tàbí “ọkàn.”
Tàbí “ẹni tí ọkàn rẹ̀ le.”
Tàbí “wọ́n pàdé bí wọ́n ṣe ṣàdéhùn?”
Tàbí “ọmọ kìnnìún tó tó ọdẹ ṣe (onígọ̀gọ̀).”
Tàbí kó jẹ́, “láìjẹ́ pé ìdẹ wà nínú rẹ̀?”
Tàbí “àṣírí rẹ̀.”
Tàbí “àga ìnàyìn ará Damásíkù.”
Tàbí “jẹ́rìí lòdì sí.”
Tàbí “ìwà ọ̀daràn.”
Tàbí kó jẹ́, “Ọ̀pọ̀ ilé.”
Tàbí “àwọn ọ̀gá.”
Tàbí “ṣọ̀tẹ̀.”
Tàbí “mi ò fún yín lóúnjẹ.”
Ìyẹn, kí nǹkan bu.
Tàbí “orin ọ̀fọ̀.”
Tàbí kó jẹ́, “ohun abàmì.”
Tàbí “ìkorò.”
Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ àwọn ìràwọ̀ Píláédì tó wà nínú àgbájọ ìràwọ̀ Tọ́rọ́sì.
Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ àgbájọ ìràwọ̀ Óríónì.
Tàbí “owó ilẹ̀.”
Tàbí “owó òde.”
Tàbí “ìwà ọ̀daràn.”
Tàbí “owó mẹ́numọ́.”
Ó ṣeé ṣe kí àwọn òrìṣà méjèèjì yìí máa tọ́ka sí pílánẹ́ẹ̀tì Sátọ̀n tí wọ́n ń sìn bí ọlọ́run.
Tàbí “tí kò mikàn.”
Ó ṣe kedere pé àwọn ìjọba ilẹ̀ Júdà àti ti Ísírẹ́lì ló ń tọ́ka sí.
Ní Héb., “jókòó.”
Tàbí “àwọn akọ ọmọ màlúù.”
Tàbí “ohun ìkọrin olókùn tín-ín-rín.”
Ní Héb., “kò mú wọn ṣàìsàn.”
Tàbí “ọkàn.”
Ní Héb., “Arákùnrin bàbá rẹ̀.”
Tàbí “ìkorò.”
Ní Héb., “la fi gba àwọn ìwo fún ara wa.”
Tàbí “àbáwọlé Hámátì.”
Ìyẹn, ní oṣù January sí February.
Ní Héb., “dìde?”
Tàbí “yí ìpinnu rẹ̀ pa dà.”
Ní Héb., “dìde?”
Tàbí “yí ìpinnu rẹ̀ pa dà.”
Ní Héb., “jẹ búrẹ́dì.”
Tàbí “ń rẹ́ ọ̀pọ̀tọ́ síkámórè.”
Wo Àfikún B14.
Wo Àfikún B14.
Tàbí “ayé.”
Tàbí “orin ọ̀fọ̀.”
Ní Héb., “aṣọ àpò ìdọ̀họ.”
Tàbí “yíyọ oòrùn.”
Tàbí “Ṣìọ́ọ̀lù,” ìyẹn ibojì aráyé. Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.
Tàbí “ayé.”
Tàbí “àgọ́; ahéré.”
Tàbí “wọn.”
Ní Héb., “máa yọ́.”