ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • nwt Nehemáyà 1:1-13:31
  • Nehemáyà

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Nehemáyà
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
Nehemáyà

NEHEMÁYÀ

1 Ọ̀rọ̀ Nehemáyà*+ ọmọ Hakaláyà nìyí: Ní oṣù Kísíléfì,* ní ogún ọdún ìṣàkóso ọba,* mo wà ní Ṣúṣánì*+ ilé ńlá.* 2 Lákòókò náà, Hánáánì,+ ọ̀kan lára àwọn arákùnrin mi pẹ̀lú àwọn ọkùnrin míì láti Júdà wá sọ́dọ̀ mi, mo sì béèrè lọ́wọ́ wọn nípa àwọn Júù tó ṣẹ́ kù, tí wọ́n yè bọ́ lóko ẹrú,+ mo tún béèrè nípa Jerúsálẹ́mù. 3 Wọ́n sọ pé: “Àwọn tó ṣẹ́ kù sí ìpínlẹ̀* Júdà, tí wọ́n yè bọ́ lóko ẹrú wà nínú ìṣòro ńlá, ìtìjú sì bá wọn.+ Àwọn ògiri Jerúsálẹ́mù ti wó lulẹ̀,+ wọ́n sì ti dáná sun àwọn ẹnubodè rẹ̀.”+

4 Nígbà tí mo gbọ́ ọ̀rọ̀ yìí, mo jókòó, mo ń sunkún, mo sì fi ọ̀pọ̀ ọjọ́ ṣọ̀fọ̀, mo bẹ̀rẹ̀ sí í gbààwẹ̀,+ mo sì ń gbàdúrà níwájú Ọlọ́run ọ̀run. 5 Mo sọ pé: “Ìwọ Jèhófà, Ọlọ́run ọ̀run, Ọlọ́run tí ó tóbi, tó sì yẹ lẹ́ni tí à ń bẹ̀rù, tó ń pa májẹ̀mú rẹ̀ mọ́, tó sì ń fi ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ hàn sí àwọn tó nífẹ̀ẹ́ rẹ̀, tí wọ́n sì ń pa àwọn àṣẹ rẹ̀ mọ́,+ 6 jọ̀ọ́, jẹ́ kí etí rẹ ṣí sílẹ̀, kí o sì bojú wò mí láti gbọ́ àdúrà ìránṣẹ́ rẹ, tí mò ń gbà sí ọ lónìí. Tọ̀sántòru ni mò ń gbàdúrà+ nítorí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ìránṣẹ́ rẹ, gbogbo ìgbà yẹn ni mò ń jẹ́wọ́ àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tí àwọn èèyàn Ísírẹ́lì dá sí ọ. A ti ṣẹ̀, àtèmi àti ilé bàbá mi.+ 7 Ó dájú pé a ti hùwà ìbàjẹ́ sí ọ,+ bí a ò ṣe pa àwọn àṣẹ àti àwọn ìlànà rẹ mọ́, tí a ò sì tẹ̀ lé àwọn ìdájọ́ rẹ, èyí tí o fún Mósè ìránṣẹ́ rẹ.+

8 “Jọ̀ọ́, rántí ọ̀rọ̀ tí o pa láṣẹ fún* Mósè ìránṣẹ́ rẹ pé: ‘Tí ẹ bá hùwà àìṣòótọ́, màá fọ́n yín ká sáàárín àwọn èèyàn orílẹ̀-èdè.+ 9 Àmọ́ tí ẹ bá pa dà sọ́dọ̀ mi, tí ẹ pa àwọn àṣẹ mi mọ́, tí ẹ sì tẹ̀ lé wọn, kódà tí àwọn èèyàn yín tí a fọ́n ká bá wà ní ìpẹ̀kun ọ̀run, màá kó wọn jọ+ láti ibẹ̀, màá sì mú wọn wá sí ibi tí mo ti yàn pé kí orúkọ mi máa wà.’+ 10 Ìránṣẹ́ rẹ ni wọ́n, èèyàn rẹ sì ni wọ́n, àwọn tí o fi agbára ńlá rẹ àti ọwọ́ agbára rẹ rà pa dà.+ 11 Ìwọ Jèhófà, jọ̀ọ́, jẹ́ kí etí rẹ ṣí sí àdúrà ìránṣẹ́ rẹ àti sí àdúrà àwọn ìránṣẹ́ rẹ tí inú wọn ń dùn láti máa bẹ̀rù orúkọ rẹ, jọ̀ọ́, jẹ́ kí ìránṣẹ́ rẹ ṣàṣeyọrí lónìí, kí ọkùnrin yìí sì ṣojú àánú sí mi.”+

Lásìkò yìí, agbọ́tí ọba ni mí.+

2 Ní oṣù Nísàn,* ní ogún ọdún + Ọba Atasásítà,+ wáìnì wà níwájú ọba, mo gbé wáìnì bí mo ti máa ń ṣe, mo sì gbé e fún ọba.+ Àmọ́ mi ò fajú ro níwájú rẹ̀ rí. 2 Ni ọba bá sọ fún mi pé: “Kí ló dé tí o fajú ro nígbà tí kì í ṣe pé ò ń ṣàìsàn? Mo mọ̀ pé ìbànújẹ́ ló mú kí o fajú ro, kì í ṣe nǹkan míì.” Ẹ̀rù sì bà mí gan-an.

3 Nígbà náà, mo sọ fún ọba pé: “Kí ẹ̀mí ọba ó gùn! Báwo ni ojú mi ò ṣe ní fà ro nígbà tí ìlú tí wọ́n sin àwọn baba ńlá mi sí ti di àwókù, tí iná sì ti jó àwọn ẹnubodè rẹ̀?”+ 4 Ọba wá sọ fún mi pé: “Kí ni ohun tí o fẹ́ gan-an?” Lójú ẹsẹ̀, mo gbàdúrà sí Ọlọ́run ọ̀run.+ 5 Mo sì sọ fún ọba pé: “Tó bá dáa lójú ọba, tí ìránṣẹ́ rẹ bá sì ti rí ojú rere rẹ, kí o rán mi lọ sí Júdà, ní ìlú tí wọ́n sin àwọn baba ńlá mi sí, kí n lè tún un kọ́.”+ 6 Ni ọba pẹ̀lú ayaba* tó jókòó lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀ bá sọ fún mi pé: “Báwo ni ìrìn àjò rẹ ṣe máa pẹ́ tó, ìgbà wo lo sì máa pa dà?” Torí náà, ó dáa lójú ọba pé kó rán mi lọ,+ mo sì dá ìgbà fún un.+

7 Lẹ́yìn náà, mo sọ fún ọba pé: “Tó bá dáa lójú ọba, jẹ́ kí wọ́n fún mi ní àwọn lẹ́tà tí màá fún àwọn gómìnà agbègbè tó wà ní Ìkọjá Odò,*+ kí wọ́n lè jẹ́ kí n kọjá títí màá fi dé Júdà 8 àti lẹ́tà tí màá fún Ásáfù tó ń ṣọ́ Ọgbà Ọba,* kó lè fún mi ní gẹdú tí màá fi ṣe òpó àwọn ẹnubodè Odi+ Ilé Ọlọ́run* àti ògiri ìlú náà+ pẹ̀lú ilé tí màá gbé.” Nítorí náà, ọba kó wọn fún mi,+ torí pé ọwọ́ rere Ọlọ́run mi wà lára mi.+

9 Nígbà tó yá, mo dé ọ̀dọ̀ àwọn gómìnà agbègbè tó wà ní Ìkọjá Odò, mo sì fún wọn ní àwọn lẹ́tà ọba. Bákan náà, ọba rán àwọn olórí ọmọ ogun àti àwọn agẹṣin tẹ̀ lé mi. 10 Nígbà tí Sáńbálátì+ ará Hórónì àti Tòbáyà + ọmọ Ámónì+ tó jẹ́ òṣìṣẹ́* ọba, gbọ́ nípa rẹ̀, inú wọn ò dùn rárá pé ẹnì kan wá láti wá ṣe ohun rere fún àwọn èèyàn Ísírẹ́lì.

11 Níkẹyìn, mo dé Jerúsálẹ́mù, mo sì lo ọjọ́ mẹ́ta níbẹ̀. 12 Mo dìde ní òru, èmi àti àwọn ọkùnrin díẹ̀ tó wà pẹ̀lú mi, mi ò sọ fún ẹnikẹ́ni nípa ohun tí Ọlọ́run mi fi sí mi lọ́kàn láti ṣe fún Jerúsálẹ́mù, kò sì sí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ kankan lọ́dọ̀ mi àfi èyí tí mo gùn. 13 Mo gba Ẹnubodè Àfonífojì+ jáde ní òru, mo kọjá níwájú Ojúsun Ejò Ńlá lọ sí Ẹnubodè Òkìtì Eérú,+ mo sì ṣàyẹ̀wò àwọn ògiri Jerúsálẹ́mù tó ti wó lulẹ̀ àti àwọn ẹnubodè rẹ̀ tí iná ti jó.+ 14 Mo kọjá lọ sí Ẹnubodè Ojúsun+ àti sí Odò Ọba, kò sì sí àyè tí ó tó fún kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ tí mo gùn láti kọjá. 15 Àmọ́ mò ń gba àfonífojì náà+ lọ ní òru, mo sì ń yẹ àwọn ògiri náà wò, lẹ́yìn èyí, mo yíjú pa dà, mo sì gba Ẹnubodè Àfonífojì wọlé, lẹ́yìn náà, mo pa dà.

16 Àwọn alábòójútó+ kò mọ ibi tí mo lọ àti ohun tí mò ń ṣe, torí mi ò tíì sọ ohunkóhun fún àwọn Júù, àwọn àlùfáà, àwọn èèyàn pàtàkì, àwọn alábòójútó àti àwọn òṣìṣẹ́ yòókù. 17 Níkẹyìn, mo sọ fún wọn pé: “Ẹ wo ìṣòro ńlá tó wà níwájú wa, bí Jerúsálẹ́mù ṣe di àwókù, tí wọ́n sì ti dáná sun àwọn ẹnubodè rẹ̀. Ẹ wá, ẹ jẹ́ ká tún ògiri Jerúsálẹ́mù mọ, ká lè bọ́ lọ́wọ́ ìtìjú tó bá wa yìí.” 18 Lẹ́yìn náà, mo sọ fún wọn nípa bí ọwọ́ rere Ọlọ́run mi ṣe wà lára mi,+ mo sì tún sọ ohun tí ọba sọ fún mi.+ Ni wọ́n bá sọ pé: “Ẹ jẹ́ ká dìde, ká sì kọ́lé.” Torí náà, wọ́n fún ara wọn níṣìírí* láti ṣe iṣẹ́ rere náà.+

19 Nígbà tí Sáńbálátì ará Hórónì àti Tòbáyà + ọmọ Ámónì+ tó jẹ́ òṣìṣẹ́ ọba* pẹ̀lú Géṣémù ọmọ ilẹ̀ Arébíà+ gbọ́ nípa rẹ̀, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í fi wá ṣe yẹ̀yẹ́,+ wọ́n sì ń fojú pa wá rẹ́, wọ́n ní: “Kí lẹ̀ ń ṣe yìí? Ẹ fẹ́ ṣọ̀tẹ̀ sí ọba, àbí?”+ 20 Àmọ́, mo fún wọn lésì pé: “Ọlọ́run ọ̀run ni Ẹni tó máa jẹ́ ká ṣàṣeyọrí,+ àwa ìránṣẹ́ rẹ̀ yóò dìde, a ó sì kọ́lé; àmọ́ ẹ̀yin ò ní ìpín kankan, bẹ́ẹ̀ ni ẹ ò ní ẹ̀tọ́ tàbí ìrántí ní Jerúsálẹ́mù.”+

3 Élíáṣíbù+ àlùfáà àgbà àti àwọn arákùnrin rẹ̀, àwọn àlùfáà, dìde láti kọ́ Ẹnubodè Àgùntàn.+ Wọ́n yà á sí mímọ́,+ wọ́n sì gbé àwọn ilẹ̀kùn rẹ̀ nàró; wọ́n yà á sí mímọ́ títí dé Ilé Gogoro Méà+ àti títí dé Ilé Gogoro Hánánélì.+ 2 Apá tó tẹ̀ lé tiwọn ni àwọn ọkùnrin Jẹ́ríkò+ mọ; Sákúrì ọmọ Ímúrì sì mọ apá tó tẹ̀ lé tiwọn.

3 Àwọn ọmọ Hásénà mọ Ẹnubodè Ẹja;+ wọ́n fi ẹ̀là gẹdú kọ́ ọ,+ lẹ́yìn náà, wọ́n gbé àwọn ilẹ̀kùn rẹ̀ sí i àti àwọn ìkọ́ rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ọ̀pá ìdábùú rẹ̀. 4 Apá tó tẹ̀ lé tiwọn ni Mérémótì + ọmọ Úríjà ọmọ Hákósì ti ṣe iṣẹ́ àtúnṣe, Méṣúlámù+ ọmọ Berekáyà ọmọ Meṣesábélì sì ṣe iṣẹ́ àtúnṣe ní apá tó tẹ̀ lé tiwọn, bákan náà Sádókù ọmọ Béánà ṣe iṣẹ́ àtúnṣe ní apá tó tẹ̀ lé tiwọn. 5 Apá tó tẹ̀ lé tiwọn ni àwọn ará Tékóà+ ti ṣe iṣẹ́ àtúnṣe, àmọ́ àwọn olókìkí àárín wọn kò rẹ ara wọn sílẹ̀ láti ṣe nínú* iṣẹ́ àwọn ọ̀gá wọn.

6 Jóyádà ọmọ Páséà àti Méṣúlámù ọmọ Besodeáyà tún Ẹnubodè Ìlú Àtijọ́+ ṣe; wọ́n fi ẹ̀là gẹdú kọ́ ọ, wọ́n sì gbé àwọn ilẹ̀kùn rẹ̀ sí i àti àwọn ìkọ́ rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ọ̀pá ìdábùú rẹ̀. 7 Apá tó tẹ̀ lé tiwọn ni Melatáyà ará Gíbíónì+ àti Jádónì ará Mérónótì ti ṣe iṣẹ́ àtúnṣe, àwọn ọkùnrin Gíbíónì àti ti Mísípà,+ tí wọ́n wà lábẹ́ àṣẹ* gómìnà agbègbè tó wà ní Ìkọjá Odò.*+ 8 Apá tó tẹ̀ lé tiwọn ni Úsíélì ọmọ Háháyà, ọ̀kan lára àwọn alágbẹ̀dẹ wúrà ti ṣe iṣẹ́ àtúnṣe, Hananáyà, ọ̀kan lára àwọn olùpo òróró ìpara,* ṣe iṣẹ́ àtúnṣe ní apá tó tẹ̀ lé tirẹ̀; wọ́n sì fi òkúta* tẹ́ ilẹ̀ Jerúsálẹ́mù títí dé Ògiri Fífẹ̀.+ 9 Apá tó tẹ̀ lé tiwọn ni Refáyà ọmọ Húrì, olórí ìdajì agbègbè Jerúsálẹ́mù ti ṣe iṣẹ́ àtúnṣe. 10 Apá tó tẹ̀ lé tiwọn ni Jedáyà ọmọ Hárúmáfù ti ṣe iṣẹ́ àtúnṣe ní iwájú ilé òun fúnra rẹ̀; Hátúṣì ọmọ Haṣabanéáyà sì ṣe iṣẹ́ àtúnṣe ní apá tó tẹ̀ lé tirẹ̀.

11 Málíkíjà ọmọ Hárímù+ àti Háṣúbù ọmọ Pahati-móábù+ tún ẹ̀ka míì* ṣe àti Ilé Gogoro Ààrò.+ 12 Apá tó tẹ̀ lé tiwọn ni Ṣálúmù ọmọ Hálóhéṣì, olórí ìdajì agbègbè Jerúsálẹ́mù ti ṣe iṣẹ́ àtúnṣe pẹ̀lú àwọn ọmọbìnrin rẹ̀.

13 Hánúnì àti àwọn tó ń gbé ní Sánóà+ tún Ẹnubodè Àfonífojì ṣe;+ wọ́n kọ́ ọ, wọ́n gbé ilẹ̀kùn rẹ̀ sí i àti àwọn ìkọ́ rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ọ̀pá ìdábùú rẹ̀, wọ́n ṣàtúnṣe ẹgbẹ̀rún (1,000) ìgbọ̀nwọ́* lára ògiri náà títí dé Ẹnubodè Òkìtì Eérú.+ 14 Málíkíjà ọmọ Rékábù, olórí ní agbègbè Bẹti-hákérémù+ tún Ẹnubodè Òkìtì Eérú ṣe; ó kọ́ ọ, ó sì gbé àwọn ilẹ̀kùn rẹ̀ sí i àti àwọn ìkọ́ rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ọ̀pá ìdábùú rẹ̀.

15 Ṣálúnì ọmọ Kólíhósè, olórí ní agbègbè Mísípà+ tún Ẹnubodè Ojúsun + ṣe; ó kọ́ ọ, ó ṣe òrùlé rẹ̀, ó sì gbé àwọn ilẹ̀kùn rẹ̀ sí i àti àwọn ìkọ́ rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ọ̀pá ìdábùú rẹ̀, ó tún ṣàtúnṣe ògiri Adágún+ Ṣélà* tó lọ sí Ọgbà Ọba+ títí dé Àtẹ̀gùn+ tó sọ̀ kalẹ̀ látinú Ìlú Dáfídì.+

16 Lẹ́yìn rẹ̀, Nehemáyà ọmọ Ásíbúkì, olórí ìdajì agbègbè Bẹti-súrì+ ṣe iṣẹ́ àtúnṣe láti iwájú Àwọn Ibi Ìsìnkú Ilé Dáfídì+ títí dé odò+ àtọwọ́dá àti títí dé Ilé Àwọn Alágbára.

17 Lẹ́yìn rẹ̀, àwọn ọmọ Léfì tó ṣe iṣẹ́ àtúnṣe nìyí: Réhúmù ọmọ Bánì; ẹni tó tẹ̀ lé e ni Haṣabáyà, olórí ìdajì agbègbè Kéílà,+ ó ṣe iṣẹ́ àtúnṣe fún agbègbè rẹ̀. 18 Lẹ́yìn rẹ̀, àwọn arákùnrin wọn tó ṣe iṣẹ́ àtúnṣe nìyí: Báfáì ọmọ Hénádádì, olórí ìdajì agbègbè Kéílà.

19 Ésérì ọmọ Jéṣúà+ tó jẹ́ olórí ní Mísípà ṣe àtúnṣe ẹ̀ka míì ní apá tó tẹ̀ lé e níwájú ìgòkè tó lọ sí Ilé Ìhámọ́ra Níbi Ìtì Ògiri.+

20 Lẹ́yìn rẹ̀, Bárúkù ọmọ Sábáì+ fi ìtara ṣiṣẹ́, ó sì tún ẹ̀ka míì ṣe, láti Ìtì Ògiri títí dé ẹnu ọ̀nà ilé Élíáṣíbù+ àlùfáà àgbà.

21 Lẹ́yìn rẹ̀, Mérémótì+ ọmọ Úríjà ọmọ Hákósì tún ẹ̀ka míì ṣe, láti ẹnu ọ̀nà ilé Élíáṣíbù títí dé òpin ilé Élíáṣíbù.

22 Lẹ́yìn rẹ̀, àwọn àlùfáà agbègbè Jọ́dánì,*+ ṣe iṣẹ́ àtúnṣe. 23 Lẹ́yìn wọn, Bẹ́ńjámínì àti Háṣúbù ṣe iṣẹ́ àtúnṣe níwájú ilé àwọn fúnra wọn. Lẹ́yìn wọn, Asaráyà ọmọ Maaseáyà ọmọ Ananíà ṣe iṣẹ́ àtúnṣe nítòsí ilé rẹ̀. 24 Lẹ́yìn rẹ̀, Bínúì ọmọ Hénádádì tún ẹ̀ka míì ṣe, láti ilé Asaráyà títí dé Ìtì Ògiri + àti títí dé igun odi.

25 Lẹ́yìn rẹ̀, Pálálì ọmọ Úṣáì ṣe iṣẹ́ àtúnṣe níwájú Ìtì Ògiri àti ilé gogoro tó yọ jáde láti Ilé Ọba,*+ ti apá òkè tó jẹ́ ti Àgbàlá Ẹ̀ṣọ́.+ Lẹ́yìn rẹ̀, ó kan Pedáyà ọmọ Páróṣì.+

26 Àwọn ìránṣẹ́ tẹ́ńpìlì*+ tí wọ́n ń gbé ní Ófélì+ ṣe iṣẹ́ àtúnṣe títí dé iwájú Ẹnubodè Omi+ ní ìlà oòrùn àti ilé gogoro tó yọ jáde náà.

27 Lẹ́yìn wọn, àwọn ará Tékóà+ tún ẹ̀ka míì ṣe, láti iwájú ilé gogoro ńlá tó yọ jáde, títí dé ògiri Ófélì.

28 Àwọn àlùfáà ṣe iṣẹ́ àtúnṣe lórí Ẹnubodè Ẹṣin,+ kálukú ṣiṣẹ́ níwájú ilé rẹ̀.

29 Lẹ́yìn wọn, Sádókù+ ọmọ Ímérì ṣe iṣẹ́ àtúnṣe níwájú ilé rẹ̀.

Ẹ̀yìn rẹ̀ ni Ṣemáyà ọmọ Ṣẹkanáyà, olùṣọ́ Ẹnubodè Ìlà Oòrùn,+ ṣe iṣẹ́ àtúnṣe.

30 Lẹ́yìn rẹ̀, Hananáyà ọmọ Ṣelemáyà àti Hánúnì ọmọ kẹfà tí Sáláfù bí tún ẹ̀ka míì ṣe.

Lẹ́yìn rẹ̀, Méṣúlámù+ ọmọ Berekáyà ṣe iṣẹ́ àtúnṣe níwájú gbọ̀ngàn òun fúnra rẹ̀.

31 Lẹ́yìn rẹ̀, Málíkíjà tó jẹ́ ọmọ ẹgbẹ́ alágbẹ̀dẹ wúrà, ṣe iṣẹ́ àtúnṣe títí dé ilé àwọn ìránṣẹ́ tẹ́ńpìlì*+ àti àwọn oníṣòwò, níwájú Ẹnubodè Àbẹ̀wò àti títí dé yàrá tó wà lórí igun odi.

32 Àárín yàrá tó wà lórí igun odi àti Ẹnubodè Àgùntàn+ sì ni àwọn alágbẹ̀dẹ wúrà àti àwọn oníṣòwò ti ṣe iṣẹ́ àtúnṣe.

4 Nígbà tí Sáńbálátì+ gbọ́ pé a ti ń tún ògiri náà mọ, ó bínú, ó fara ya,* ó sì ń fi àwọn Júù ṣe yẹ̀yẹ́. 2 Ó wá sọ níṣojú àwọn arákùnrin rẹ̀ àti àwọn ọmọ ogun Samáríà pé: “Kí ni àwọn Júù aláìlera yìí ń ṣe? Ṣé wọ́n lè dá a ṣe ni? Ṣé wọ́n fẹ́ máa rúbọ ni? Ṣé wọ́n lè parí rẹ̀ lọ́jọ́ kan ni? Ṣé wọ́n lè mú kí àwọn òkúta jíjóná tó wà nínú àwọn òkìtì àwókù di èyí tó ṣeé lò ni?”+

3 Lásìkò náà, Tòbáyà+ ọmọ Ámónì+ tó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀ sọ pé: “Kódà tí kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ bá gun ohun tí wọ́n ń kọ́, ó máa wó ògiri olókùúta wọn lulẹ̀.”

4 Gbọ́, ìwọ Ọlọ́run wa, nítorí wọ́n ń kàn wá lábùkù,+ dá ẹ̀gàn wọn pa dà sórí wọn,+ jẹ́ kí wọ́n dà bí ẹrù ogun, kí wọ́n sì di ẹrú ní ilẹ̀ àjèjì. 5 Má ṣe bo àṣìṣe wọn mọ́lẹ̀ tàbí kí o jẹ́ kí ẹ̀ṣẹ̀ wọn pa rẹ́ níwájú rẹ,+ nítorí wọ́n ti sọ̀rọ̀ burúkú sí àwọn tó ń mọ ògiri náà.

6 Torí náà, à ń mọ ògiri náà lọ, a sì mọ gbogbo rẹ̀ kan ara wọn, títí ó fi dé ìdajì gíga rẹ̀, àwọn èèyàn náà sì fọkàn sí iṣẹ́ náà.

7 Nígbà tí Sáńbálátì, Tòbáyà,+ àwọn ọmọ ilẹ̀ Arébíà+ àti àwọn ọmọ Ámónì pẹ̀lú àwọn ará Áṣídódì+ gbọ́ pé àtúnṣe ògiri Jerúsálẹ́mù ń lọ déédéé àti pé a ti ń dí àwọn àlàfo rẹ̀, inú bí wọn gidigidi. 8 Wọ́n gbìmọ̀ pọ̀ láti dojú ìjà kọ Jerúsálẹ́mù, kí wọ́n sì dá rúkèrúdò sílẹ̀. 9 Àmọ́, a gbàdúrà sí Ọlọ́run wa, a sì yan ẹ̀ṣọ́ láti máa ṣọ́ wa tọ̀sántòru nítorí wọn.

10 Síbẹ̀, àwọn èèyàn Júdà ń sọ pé: “Àwọn lébìrà* ò lágbára mọ́, àwókù tó wà nílẹ̀ sì pọ̀ gan-an; a ò lè mọ ògiri náà láé.”

11 Àwọn ọ̀tá wa sì ń sọ pé: “Kí wọ́n tó mọ̀ tàbí kí wọ́n tó rí wa, a ó wọ àárín wọn, a ó pa wọ́n, a ó sì dá iṣẹ́ náà dúró.”

12 Ìgbàkígbà tí àwọn Júù tó ń gbé nítòsí wọn bá wá, wọ́n máa ń sọ fún wa léraléra* pé: “Kò síbi tí wọn ò ní gbà yọ sí wa.”

13 Torí náà, mo fi àwọn ọkùnrin kan sí apá ìsàlẹ̀ pátápátá níbi gbayawu tó wà lẹ́yìn ògiri náà, mo sì yàn wọ́n ní ìdílé-ìdílé, wọ́n mú idà wọn, aṣóró wọn àti ọfà* wọn lọ́wọ́. 14 Nígbà tí mo rí i pé ẹ̀rù ń bà wọ́n, ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ni mo dìde, mo sì sọ fún àwọn èèyàn pàtàkì+ àti àwọn alábòójútó pẹ̀lú àwọn èèyàn yòókù pé: “Ẹ má bẹ̀rù wọn.+ Ẹ rántí Jèhófà, ẹni gíga tó yẹ ká máa bẹ̀rù;+ ẹ jà fún àwọn arákùnrin yín, àwọn ọmọkùnrin yín àti àwọn ọmọbìnrin yín pẹ̀lú àwọn ìyàwó yín àti ilé yín.”

15 Lẹ́yìn tí àwọn ọ̀tá wa gbọ́ pé a ti mọ ohun tí wọ́n ń ṣe àti pé Ọlọ́run tòótọ́ ti sọ èrò wọn dasán, gbogbo wa pa dà sẹ́nu iṣẹ́ ògiri náà. 16 Látọjọ́ yẹn lọ, ìdajì àwọn ọkùnrin mi ló ń ṣe iṣẹ́ náà,+ ìdajì yòókù á mú aṣóró, apata àti ọfà* dání, wọ́n á sì wọ ẹ̀wù irin. Bákan náà, àwọn olórí+ wà lẹ́yìn gbogbo èèyàn ilé Júdà 17 tí wọ́n ń mọ ògiri náà. Àwọn tó ń ru ẹrù ń fi ọwọ́ kan ṣiṣẹ́, wọ́n á sì fi ọwọ́ kejì di ohun ìjà* mú. 18 Kọ́lékọ́lé kọ̀ọ̀kan de idà mọ́ ìbàdí rẹ̀ bó ṣe ń mọlé, ẹni tó sì máa fun ìwo+ dúró lẹ́gbẹ̀ẹ́ mi.

19 Mo wá sọ fún àwọn èèyàn pàtàkì àti àwọn alábòójútó pẹ̀lú àwọn èèyàn yòókù pé: “Iṣẹ́ náà pọ̀, ó sì gbòòrò, a wà lórí ògiri náà káàkiri, a sì jìnnà sí ara wa. 20 Tí ẹ bá ti gbọ́ ìró ìwo, kí ẹ kóra jọ sọ́dọ̀ wa. Ọlọ́run wa yóò jà fún wa.”+

21 Torí náà, à ń bá iṣẹ́ lọ, àwọn ìdajì yòókù sì di aṣóró mú, látìgbà tí ilẹ̀ bá ti mọ́ títí ìràwọ̀ á fi yọ. 22 Lákòókò yẹn, mo sọ fún àwọn èèyàn náà pé: “Kí ọkùnrin kọ̀ọ̀kan pẹ̀lú ìránṣẹ́ rẹ̀ dúró sí Jerúsálẹ́mù mọ́jú, wọ́n á máa ṣọ́ wa ní òru, wọ́n á sì máa ṣiṣẹ́ lọ́sàn-án.” 23 Torí náà, nínú èmi àti àwọn arákùnrin mi pẹ̀lú àwọn ìránṣẹ́ mi+ àti àwọn ẹ̀ṣọ́ tó tẹ̀ lé mi, kò sẹ́ni tó bọ́ ẹ̀wù rẹ̀ sílẹ̀, ohun ìjà kò sì kúrò lọ́wọ́ ọ̀tún kálukú wa.

5 Àwọn èèyàn náà àti àwọn ìyàwó wọn gbé ohùn wọn sókè, wọ́n sì ń sunkún nítorí ohun tí àwọn Júù, arákùnrin wọn ń ṣe.+ 2 Àwọn kan ń sọ pé: “Àwa àti àwọn ọmọkùnrin wa pẹ̀lú àwọn ọmọbìnrin wa pọ̀. A gbọ́dọ̀ rí oúnjẹ* tí a máa jẹ, kí a má bàa kú.” 3 Àwọn míì ń sọ pé: “Àwọn oko wa àti àwọn ọgbà àjàrà wa pẹ̀lú àwọn ilé wa la fi ṣe ohun ìdúró, ká lè rí ọkà lásìkò tí kò sí oúnjẹ.” 4 Àwọn míì sì tún ń sọ pé: “A ti fi àwọn oko wa àti àwọn ọgbà àjàrà wa yá owó ká lè rí ìṣákọ́lẹ̀* ọba san.+ 5 Ara kan náà àti ẹ̀jẹ̀ kan náà ni àwa àti àwọn arákùnrin wa,* bí àwọn ọmọ wọn ṣe rí náà ni àwọn ọmọ wa rí; síbẹ̀ a ní láti sọ àwọn ọmọkùnrin wa àti àwọn ọmọbìnrin wa di ẹrú, kódà lára àwọn ọmọbìnrin wa ti di ẹrú.+ Àmọ́, a ò ní agbára kankan láti dá èyí dúró, nítorí àwọn oko wa àti àwọn ọgbà àjàrà wa ti di ti àwọn ẹlòmíì.”

6 Inú bí mi gan-an nígbà tí mo gbọ́ igbe ẹkún wọn àti ọ̀rọ̀ yìí. 7 Nítorí náà, mo ro gbogbo rẹ̀ lọ́kàn mi, mo sì bá àwọn èèyàn pàtàkì àti àwọn alábòójútó wí, mo sọ fún wọn pé: “Kálukú yín ń gba èlé* lọ́wọ́ arákùnrin rẹ̀.”+

Yàtọ̀ síyẹn, mo ṣètò àpéjọ ńlá kan nítorí wọn. 8 Mo sọ fún wọn pé: “A ti ra àwọn Júù arákùnrin wa tí wọ́n tà fún àwọn orílẹ̀-èdè pa dà débi tí agbára wa gbé e dé; àmọ́, ṣé ẹ máa wá ta àwọn arákùnrin yín ni,+ ṣé ó yẹ ká tún rà wọ́n pa dà lọ́wọ́ yín ni?” Ni kẹ́kẹ́ bá pa mọ́ wọn lẹ́nu, wọn ò sì rí nǹkan kan sọ. 9 Lẹ́yìn náà, mo sọ pé: “Ohun tí ẹ̀ ń ṣe yìí kò dára. Ṣé kò yẹ kí ẹ máa rìn nínú ìbẹ̀rù Ọlọ́run wa+ kí àwọn orílẹ̀-èdè, ìyẹn àwọn ọ̀tá wa má bàa pẹ̀gàn wa ni? 10 Yàtọ̀ síyẹn, èmi àti àwọn arákùnrin mi pẹ̀lú àwọn ìránṣẹ́ mi ń yá wọn ní owó àti ọkà. Ẹ jọ̀ọ́, ẹ jẹ́ ká jáwọ́ nínú gbígba èlé lórí ohun tí a yáni.+ 11 Ẹ jọ̀ọ́, ẹ dá àwọn nǹkan tí ẹ ti gbà pa dà fún wọn lónìí,+ ìyẹn ilẹ̀ wọn, ọgbà àjàrà wọn, oko ólífì wọn àti ilé wọn, títí kan ìdá ọgọ́rùn-ún* owó, ọkà, wáìnì tuntun àti òróró tí ẹ̀ ń gbà lọ́wọ́ wọn gẹ́gẹ́ bí èlé.”

12 Wọ́n wá fèsì pé: “A máa dá nǹkan wọ̀nyí pa dà fún wọn, a ò sì ní béèrè ohunkóhun pa dà. A máa ṣe ohun tí o sọ.” Torí náà, mo pe àwọn àlùfáà, mo sì mú kí wọ́n búra pé wọ́n á mú ìlérí yìí ṣẹ. 13 Mo tún gbọn ibi tó ṣẹ́ po lára aṣọ* mi jáde, mo sì sọ pé: “Ní ọ̀nà yìí, kí Ọlọ́run tòótọ́ gbọn gbogbo ẹni tí kò bá mú ìlérí yìí ṣẹ kúrò nínú ilé rẹ̀ àti kúrò nínú ohun ìní rẹ̀, ọ̀nà yìí sì ni kí a gbà gbọ̀n ọ́n dà nù kí ó sì di òfo.” Gbogbo ìjọ fèsì pé: “Àmín!”* Wọ́n yin Jèhófà, àwọn èèyàn náà sì ṣe ohun tí wọ́n ṣèlérí.

14 Bákan náà, láti ọjọ́ tí ọba ti yàn mí láti di gómìnà wọn+ ní ilẹ̀ Júdà, láti ogún ọdún+ sí ọdún kejìlélọ́gbọ̀n+ Ọba Atasásítà,+ ó jẹ́ ọdún méjìlá (12), èmi àti àwọn arákùnrin mi kò jẹ oúnjẹ tó yẹ gómìnà.+ 15 Àmọ́, àwọn gómìnà tó wà ṣáájú mi ti di ẹrù tó wúwo sórí àwọn èèyàn náà, wọ́n sì ń gba ogójì (40) ṣékélì* fàdákà lọ́wọ́ wọn fún oúnjẹ àti wáìnì lójoojúmọ́. Àwọn ìránṣẹ́ wọn tún ń ni àwọn èèyàn lára. Ṣùgbọ́n mi ò ṣe bẹ́ẹ̀+ nítorí ìbẹ̀rù Ọlọ́run.+

16 Yàtọ̀ síyẹn, mo ṣe nínú iṣẹ́ ògiri yìí, gbogbo àwọn ìránṣẹ́ mi kóra jọ síbẹ̀ fún iṣẹ́ náà, a kò sì gba ilẹ̀ kankan.+ 17 Àádọ́jọ (150) Júù àti àwọn alábòójútó ló ń jẹun lórí tábìlì mi, títí kan àwọn tó wá sọ́dọ̀ wa látinú àwọn orílẹ̀-èdè. 18 Lójoojúmọ́, akọ màlúù kan, àgùntàn mẹ́fà tó dáa àti àwọn ẹyẹ* ni wọ́n ń pa fún mi,* a sì máa ń pèsè ọ̀pọ̀ wáìnì lóríṣiríṣi lẹ́ẹ̀kan lọ́jọ́ mẹ́wàá. Síbẹ̀, mi ò béèrè oúnjẹ tó yẹ gómìnà, nítorí pé iṣẹ́ tó wà lọ́rùn àwọn èèyàn náà pọ̀, ó sì ti wọ̀ wọ́n lọ́rùn. 19 Ọlọ́run mi, jọ̀wọ́ rántí mi sí rere* lórí gbogbo ohun tí mo ti ṣe nítorí àwọn èèyàn yìí.+

6 Nígbà tí wọ́n sọ fún Sáńbálátì, Tòbáyà+ àti Géṣémù ọmọ ilẹ̀ Arébíà+ pẹ̀lú àwọn ọ̀tá wa yòókù pé mo ti tún ògiri náà kọ́+ àti pé kò sí àlàfo kankan tó ṣẹ́ kù lára rẹ̀ (bó tilẹ̀ jẹ́ pé títí di àkókò yẹn, mi ò tíì gbé ilẹ̀kùn sí àwọn ẹnubodè),+ 2 ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ni Sáńbálátì àti Géṣémù ránṣẹ́ sí mi pé: “Wá, jẹ́ ká dá ìgbà tí a jọ máa pàdé ní àwọn abúlé tó wà ní Pẹ̀tẹ́lẹ̀ Ónò.”+ Àmọ́ ṣe ni wọ́n ń gbèrò láti ṣe mí ní ibi. 3 Torí náà, mo rán àwọn òjíṣẹ́ sí wọn pé: “Iṣẹ́ ńlá ni mò ń ṣe, mi ò sì lè wá. Ṣé ó yẹ kí iṣẹ́ náà dúró torí pé mo fi í sílẹ̀ láti wá bá yín?” 4 Wọ́n rán iṣẹ́ kan náà sí mi nígbà mẹ́rin, èsì kan náà ni mo sì ń fún wọn.

5 Ni Sáńbálátì bá tún fi iṣẹ́ kan náà rán ìránṣẹ́ rẹ̀ sí mi nígbà karùn-ún tòun ti lẹ́tà kan tí wọn ò lẹ̀. 6 Wọ́n kọ ọ́ sínú rẹ̀ pé: “A ti gbọ́ láàárín àwọn orílẹ̀-èdè, Géṣémù+ sì ń sọ ọ́ pé, ìwọ àti àwọn Júù ń gbèrò láti dìtẹ̀.+ Ìdí nìyẹn tí o fi ń mọ ògiri náà; ohun tí wọ́n ń sọ sì fi hàn pé ìwọ lo máa di ọba wọn. 7 Bákan náà, o ti yan àwọn wòlíì láti kéde nípa rẹ káàkiri Jerúsálẹ́mù pé, ‘Ọba kan wà ní Júdà!’ Wò ó, gbogbo ọ̀rọ̀ yìí ló máa dé etí ọba. Torí náà, wá, jẹ́ ká jọ sọ ọ̀rọ̀ yìí láàárín ara wa.”

8 Àmọ́, èsì tí mo fi ránṣẹ́ sí i nìyí: “Kò sí ìkankan nínú gbogbo ohun tí o sọ tó ṣẹlẹ̀, ohun tí o gbèrò lọ́kàn ara rẹ lò ń sọ.” 9 Gbogbo wọn ló fẹ́ máa dẹ́rù bà wá, wọ́n ń sọ pé: “Wọ́n á dẹwọ́ lẹ́nu iṣẹ́ náà, wọn ò sì ní parí rẹ̀.”+ Ní báyìí, mo gbàdúrà, jọ̀wọ́ fún mi lókun.+

10 Mo wá lọ sí ilé Ṣemáyà ọmọ Deláyà ọmọ Méhétábélì nígbà tó wà ní àhámọ́ níbẹ̀. Ó sọ fún mi pé: “Jẹ́ ká dá ìgbà tí a jọ máa pàdé ní ilé Ọlọ́run tòótọ́, nínú tẹ́ńpìlì, ká sì ti àwọn ilẹ̀kùn tẹ́ńpìlì, nítorí wọ́n ń bọ̀ wá pa ọ́. Òru ni wọ́n máa wá pa ọ́.” 11 Àmọ́ mo sọ pé: “Ṣé irú mi ló yẹ kó sá lọ? Ṣé irú mi lè wọnú tẹ́ńpìlì, kí n má sì kú?+ Mi ò ní wọ ibẹ̀!” 12 Ìgbà náà ni mo rí i pé, kì í ṣe Ọlọ́run ló rán an, Tòbáyà àti Sáńbálátì+ ló lọ gbà á pé kó sọ àsọtẹ́lẹ̀ yìí sí mi. 13 Ńṣe ni wọ́n gbà á kó lè dẹ́rù bà mí, kí n sì dẹ́ṣẹ̀, kí wọ́n lè rí ẹ̀sùn tí wọ́n á fi bà mí lórúkọ jẹ́, kí wọ́n sì fi mí ṣẹ̀sín.

14 Ọlọ́run mi, rántí Tòbáyà+ àti Sáńbálátì àti ohun tí wọ́n ṣe yìí, tún rántí Noadáyà wòlíì obìnrin àti àwọn wòlíì yòókù tó ń dẹ́rù bà mí nígbà gbogbo.

15 Nítorí náà, ọjọ́ méjìléláàádọ́ta (52) la fi mọ ògiri náà, ó sì parí ní ọjọ́ kẹẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n oṣù Élúlì.*

16 Nígbà tí gbogbo àwọn ọ̀tá wa gbọ́, tí gbogbo orílẹ̀-èdè tó yí wa ká sì rí i, ìtìjú ńlá* bá wọn,+ wọ́n sì rí i pé Ọlọ́run wa ló ràn wá lọ́wọ́ tí a fi lè parí iṣẹ́ náà. 17 Lákòókò yẹn, àwọn èèyàn pàtàkì+ ní Júdà ń fi ọ̀pọ̀ lẹ́tà ránṣẹ́ sí Tòbáyà, Tòbáyà sì ń dá èsì pa dà. 18 Ọ̀pọ̀ àwọn tó wà ní Júdà búra pé ẹ̀yìn rẹ̀ làwọn wà, torí pé ó jẹ́ àna Ṣẹkanáyà ọmọ Áráhì,+ Jèhóhánánì ọmọ rẹ̀ sì fẹ́ ọmọbìnrin Méṣúlámù+ ọmọ Berekáyà. 19 Bákan náà, ìgbà gbogbo ni wọ́n máa ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ dáadáa lójú mi, wọ́n á sì lọ sọ ohun tí mo bá fi fèsì fún un. Tòbáyà á wá kọ àwọn lẹ́tà sí mi láti fi dẹ́rù bà mí.+

7 Nígbà tí a tún ògiri náà mọ tán,+ mo gbé àwọn ilẹ̀kùn sí i;+ lẹ́yìn náà, a yan àwọn aṣọ́bodè,+ àwọn akọrin+ àti àwọn ọmọ Léfì.+ 2 Mo wá ní kí Hánáánì+ arákùnrin mi máa bójú tó Jerúsálẹ́mù pẹ̀lú Hananáyà olórí Ibi Ààbò,+ torí òun ló ṣe é fọkàn tán jù lọ, ó sì bẹ̀rù Ọlọ́run tòótọ́+ ju ọ̀pọ̀ àwọn míì lọ. 3 Torí náà, mo sọ fún wọn pé: “Àwọn aṣọ́bodè kò gbọ́dọ̀ ṣí àwọn ẹnubodè Jerúsálẹ́mù títí ọ̀sán á fi pọ́n. Kí wọ́n tó kúrò lẹ́nu iṣẹ́, kí wọ́n ti àwọn ilẹ̀kùn, kí wọ́n sì fi ìkọ́ há wọn. Kí wọ́n yan àwọn ẹ̀ṣọ́ lára àwọn tó ń gbé Jerúsálẹ́mù, kálukú sí ibi ìṣọ́ tí wọ́n yàn án sí, kí kálukú sì wà níwájú ilé rẹ̀.” 4 Ìlú náà tóbi, ó sì fẹ̀, àmọ́ àwọn tó wà nínú rẹ̀ kò pọ̀,+ wọn ò sì tíì tún àwọn ilé tó wà nínú rẹ̀ kọ́.

5 Ṣùgbọ́n Ọlọ́run mi fi sí mi lọ́kàn pé kí n kó àwọn èèyàn pàtàkì àti àwọn alábòójútó pẹ̀lú àwọn èèyàn náà jọ láti kọ orúkọ wọn sílẹ̀ bí wọ́n ṣe wà nínú ìdílé wọn.+ Nígbà náà, mo rí ìwé àkọsílẹ̀ ìdílé àwọn tó kọ́kọ́ jáde wá, mo sì rí i pé a kọ ọ́ sínú rẹ̀ pé:

6 Àwọn yìí ni àwọn èèyàn ìpínlẹ̀* tí wọ́n pa dà lára àwọn tó wà nígbèkùn, àwọn tí Nebukadinésárì+ ọba Bábílónì kó lọ sí ìgbèkùn,+ àmọ́ tí wọ́n pa dà sí Jerúsálẹ́mù àti Júdà nígbà tó yá, kálukú pa dà sí ìlú rẹ̀,+ 7 àwọn tí wọ́n tẹ̀ lé ni Serubábélì,+ Jéṣúà,+ Nehemáyà, Asaráyà, Raamáyà, Náhámánì, Módékáì, Bílíṣánì, Mísípérétì, Bígífáì, Néhúmù àti Báánà.

Iye àwọn ọkùnrin tí wọ́n jẹ́ ọmọ Ísírẹ́lì nìyí:+ 8 àwọn ọmọ Páróṣì jẹ́ ẹgbẹ̀rún méjì ó lé méjìléláàádọ́sàn-án (2,172); 9 àwọn ọmọ Ṣẹfatáyà jẹ́ ọgọ́rùn-ún mẹ́ta ó lé méjìléláàádọ́rin (372); 10 àwọn ọmọ Áráhì+ jẹ́ ọgọ́rùn-ún mẹ́fà ó lé méjìléláàádọ́ta (652); 11 àwọn ọmọ Pahati-móábù,+ látinú àwọn ọmọ Jéṣúà àti Jóábù+ jẹ́ ẹgbẹ̀rún méjì ó lé ọgọ́rùn-ún mẹ́jọ àti méjìdínlógún (2,818); 12 àwọn ọmọ Élámù+ jẹ́ ẹgbẹ̀rún kan ó lé igba àti mẹ́rìnléláàádọ́ta (1,254); 13 àwọn ọmọ Sátù jẹ́ ọgọ́rùn-ún mẹ́jọ ó lé márùnlélógójì (845); 14 àwọn ọmọ Sákáì jẹ́ ọgọ́rùn-ún méje ó lé ọgọ́ta (760); 15 àwọn ọmọ Bínúì jẹ́ ọgọ́rùn-ún mẹ́fà ó lé méjìdínláàádọ́ta (648); 16 àwọn ọmọ Bébáì jẹ́ ọgọ́rùn-ún mẹ́fà ó lé méjìdínlọ́gbọ̀n (628); 17 àwọn ọmọ Ásígádì jẹ́ ẹgbẹ̀rún méjì ó lé ọgọ́rùn-ún mẹ́ta àti méjìlélógún (2,322); 18 àwọn ọmọ Ádóníkámù jẹ́ ọgọ́rùn-ún mẹ́fà ó lé mẹ́tàdínláàádọ́rin (667); 19 àwọn ọmọ Bígífáì jẹ́ ẹgbẹ̀rún méjì ó lé mẹ́tàdínláàádọ́rin (2,067); 20 àwọn ọmọ Ádínì jẹ́ ọgọ́rùn-ún mẹ́fà ó lé márùndínlọ́gọ́ta (655); 21 àwọn ọmọ Átérì láti ilé Hẹsikáyà jẹ́ méjìdínlọ́gọ́rùn-ún (98); 22 àwọn ọmọ Háṣúmù jẹ́ ọgọ́rùn-ún mẹ́ta ó lé méjìdínlọ́gbọ̀n (328); 23 àwọn ọmọ Bísáì jẹ́ ọgọ́rùn-ún mẹ́ta ó lé mẹ́rìnlélógún (324); 24 àwọn ọmọ Hárífù jẹ́ méjìléláàádọ́fà (112); 25 àwọn ọmọ Gíbíónì+ jẹ́ márùndínlọ́gọ́rùn-ún (95); 26 àwọn ọkùnrin Bẹ́tílẹ́hẹ́mù àti Nétófà jẹ́ ọgọ́sàn-án ó lé mẹ́jọ (188); 27 àwọn ọkùnrin Ánátótì+ jẹ́ méjìdínláàádóje (128); 28 àwọn ọkùnrin Bẹti-ásímáfẹ́tì jẹ́ méjìlélógójì (42); 29 àwọn ọkùnrin Kiriati-jéárímù,+ Kéfírà àti Béérótì+ jẹ́ ọgọ́rùn-ún méje ó lé mẹ́tàlélógójì (743); 30 àwọn ọkùnrin Rámà àti Gébà+ jẹ́ ọgọ́rùn-ún mẹ́fà ó lé mọ́kànlélógún (621); 31 àwọn ọkùnrin Míkímásì+ jẹ́ méjìlélọ́gọ́fà (122); 32 àwọn ọkùnrin Bẹ́tẹ́lì+ àti Áì+ jẹ́ mẹ́tàlélọ́gọ́fà (123); 33 àwọn ọkùnrin Nébò kejì jẹ́ méjìléláàádọ́ta (52); 34 àwọn ọmọ Élámù kejì jẹ́ ẹgbẹ̀rún kan ó lé igba àti mẹ́rìnléláàádọ́ta (1,254); 35 àwọn ọmọ Hárímù jẹ́ ọgọ́rùn-ún mẹ́ta ó lé ogún (320); 36 àwọn ọmọ Jẹ́ríkò jẹ́ ọgọ́rùn-ún mẹ́ta ó lé márùnlélógójì (345); 37 àwọn ọmọ Lódì, Hádídì àti Ónò+ jẹ́ ọgọ́rùn-ún méje ó lé mọ́kànlélógún (721); 38 àwọn ọmọ Sénáà jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́ta ó lé ọgọ́rùn-ún mẹ́sàn-án àti ọgbọ̀n (3,930).

39 Àwọn àlùfáà nìyí:+ àwọn ọmọ Jedáyà láti ilé Jéṣúà jẹ́ ọgọ́rùn-ún mẹ́sàn-án ó lé mẹ́tàléláàádọ́rin (973); 40 àwọn ọmọ Ímérì jẹ́ ẹgbẹ̀rún kan ó lé méjìléláàádọ́ta (1,052); 41 àwọn ọmọ Páṣúrì+ jẹ́ ẹgbẹ̀rún kan ó lé igba àti mẹ́tàdínláàádọ́ta (1,247); 42 àwọn ọmọ Hárímù+ jẹ́ ẹgbẹ̀rún kan ó lé mẹ́tàdínlógún (1,017).

43 Àwọn ọmọ Léfì nìyí:+ àwọn ọmọ Jéṣúà, ti Kádímíélì,+ ti àwọn ọmọ Hódéfà jẹ́ mẹ́rìnléláàádọ́rin (74); 44 Àwọn akọrin nìyí:+ àwọn ọmọ Ásáfù,+ wọ́n jẹ́ méjìdínláàádọ́jọ (148). 45 Àwọn aṣọ́bodè nìyí:+ àwọn ọmọ Ṣálúmù, àwọn ọmọ Átérì, àwọn ọmọ Tálímónì, àwọn ọmọ Ákúbù,+ àwọn ọmọ Hátítà, àwọn ọmọ Ṣóbáì, gbogbo wọn jẹ́ méjìdínlógóje (138).

46 Àwọn ìránṣẹ́ tẹ́ńpìlì* nìyí:+ àwọn ọmọ Síhà, àwọn ọmọ Hásúfà, àwọn ọmọ Tábáótì, 47 àwọn ọmọ Kérósì, àwọn ọmọ Síà, àwọn ọmọ Pádónì, 48 àwọn ọmọ Lébánà, àwọn ọmọ Hágábà, àwọn ọmọ Sálímáì, 49 àwọn ọmọ Hánánì, àwọn ọmọ Gídélì, àwọn ọmọ Gáhárì, 50 àwọn ọmọ Reáyà, àwọn ọmọ Résínì, àwọn ọmọ Nékódà, 51 àwọn ọmọ Gásámù, àwọn ọmọ Úúsà, àwọn ọmọ Páséà, 52 àwọn ọmọ Bésáì, àwọn ọmọ Méúnímù, àwọn ọmọ Néfúṣésímù, 53 àwọn ọmọ Bákíbúkì, àwọn ọmọ Hákúfà, àwọn ọmọ Háhúrì, 54 àwọn ọmọ Básílítì, àwọn ọmọ Méhídà, àwọn ọmọ Háṣà, 55 àwọn ọmọ Bákósì, àwọn ọmọ Sísérà, àwọn ọmọ Téémà, 56 àwọn ọmọ Nesáyà àti àwọn ọmọ Hátífà.

57 Àwọn ọmọ àwọn ìránṣẹ́ Sólómọ́nì nìyí:+ àwọn ọmọ Sótáì, àwọn ọmọ Sóférétì, àwọn ọmọ Pérídà, 58 àwọn ọmọ Jáálà, àwọn ọmọ Dákónì, àwọn ọmọ Gídélì, 59 àwọn ọmọ Ṣẹfatáyà, àwọn ọmọ Hátílì, àwọn ọmọ Pokereti-hásébáímù, àwọn ọmọ Ámọ́nì. 60 Gbogbo àwọn ìránṣẹ́ tẹ́ńpìlì*+ àti ọmọ àwọn ìránṣẹ́ Sólómọ́nì jẹ́ ọgọ́rùn-ún mẹ́ta ó lé àádọ́rùn-ún àti méjì (392).

61 Àwọn tó lọ láti Tẹli-mélà, Tẹli-háṣà, Kérúbù, Ádónì àti Ímérì, àmọ́ tí wọn kò lè sọ agbo ilé bàbá wọn àti ibi tí wọ́n ti ṣẹ̀ wá láti fi hàn pé ọmọ Ísírẹ́lì ni wọ́n nìyí:+ 62 àwọn ọmọ Deláyà, àwọn ọmọ Tòbáyà àti àwọn ọmọ Nékódà, wọ́n jẹ́ ọgọ́rùn-ún mẹ́fà ó lé méjìlélógójì (642). 63 Látinú àwọn àlùfáà: àwọn ọmọ Habáyà, àwọn ọmọ Hákósì,+ àwọn ọmọ Básíláì tó fẹ́ ọ̀kan lára àwọn ọmọbìnrin Básíláì+ ọmọ Gílíádì, tó sì wá ń jẹ́ orúkọ wọn. 64 Wọ́n wá àkọsílẹ̀ wọn láti mọ ìdílé tí wọ́n ti wá, àmọ́ wọn kò rí i, torí náà, wọn ò gbà kí wọ́n ṣiṣẹ́ àlùfáà.*+ 65 Gómìnà*+ sọ fún wọn pé wọn ò gbọ́dọ̀ jẹ lára àwọn ohun mímọ́ jù lọ,+ títí wọ́n á fi rí àlùfáà tó máa bá wọn fi Úrímù àti Túmímù+ wádìí.

66 Iye gbogbo ìjọ náà jẹ́ ẹgbẹ̀rún méjìlélógójì ó lé ọgọ́rùn-ún mẹ́ta àti ọgọ́ta (42,360),+ 67 yàtọ̀ sí àwọn ẹrúkùnrin àti ẹrúbìnrin wọn,+ tí iye wọn jẹ́ ẹgbẹ̀rún méje ó lé ọgọ́rùn-ún mẹ́ta àti mẹ́tàdínlógójì (7,337); wọ́n tún ní àwọn akọrin lọ́kùnrin àti lóbìnrin+ tí wọ́n jẹ́ igba ó lé márùnlélógójì (245). 68 Ẹṣin wọn jẹ́ ọgọ́rùn-ún méje ó lé mẹ́rìndínlógójì (736), ìbaaka wọn jẹ́ igba ó lé márùnlélógójì (245), 69 ràkúnmí wọn jẹ́ ọgọ́rùn-ún mẹ́rin ó lé márùndínlógójì (435), kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ wọn jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́fà ó lé ọgọ́rùn-ún méje àti ogún (6,720).

70 Lára àwọn olórí agbo ilé mú ọrẹ wá fún iṣẹ́ náà.+ Gómìnà* mú ẹgbẹ̀rún kan (1,000) owó dírákímà* wúrà, àádọ́ta (50) abọ́ àti ọgọ́rùn-ún márùn-ún ó lé ọgbọ̀n (530) aṣọ àwọn àlùfáà+ wá sí ibi ìṣúra. 71 Lára àwọn olórí agbo ilé mú ọ̀kẹ́ kan (20,000) owó dírákímà wúrà àti ẹgbẹ̀rún méjì ó lé igba (2,200) mínà* fàdákà wá sí ibi ìṣúra iṣẹ́ ilé náà. 72 Àwọn èèyàn yòókù sì mú ọ̀kẹ́ kan (20,000) owó dírákímà wúrà àti ẹgbẹ̀rún méjì (2,000) mínà fàdákà àti àádọ́rin dín mẹ́ta (67) aṣọ àwọn àlùfáà wá.

73 Àwọn àlùfáà, àwọn ọmọ Léfì, àwọn aṣọ́bodè, àwọn akọrin,+ àwọn kan lára àwọn èèyàn náà àti àwọn ìránṣẹ́ tẹ́ńpìlì* pẹ̀lú gbogbo ọmọ Ísírẹ́lì yòókù* bẹ̀rẹ̀ sí í gbé inú àwọn ìlú wọn.+ Nígbà tó fi máa di oṣù keje,+ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ti wà nínú àwọn ìlú wọn.+

8 Gbogbo àwọn èèyàn náà kóra jọ ní ìṣọ̀kan sí gbàgede ìlú tó wà níwájú Ẹnubodè Omi,+ wọ́n sì sọ fún Ẹ́sírà+ adàwékọ* pé kó mú ìwé Òfin Mósè+ wá, èyí tí Jèhófà pa láṣẹ fún Ísírẹ́lì.+ 2 Torí náà, ní ọjọ́ kìíní oṣù keje,+ àlùfáà Ẹ́sírà mú ìwé Òfin náà wá síwájú àpéjọ*+ àwọn ọkùnrin àti àwọn obìnrin pẹ̀lú gbogbo àwọn tó lè lóye ohun tí wọ́n bá gbọ́. 3 Ó sì kà á sókè+ ní gbàgede ìlú tó wà níwájú Ẹnubodè Omi, láti àfẹ̀mọ́jú títí di ọ̀sán gangan, fún àwọn ọkùnrin àti àwọn obìnrin àti gbogbo àwọn tí ọ̀rọ̀ náà lè yé; gbogbo àwọn èèyàn náà sì fetí sílẹ̀ dáadáa+ sí ìwé Òfin náà. 4 Ẹ́sírà adàwékọ* dúró lórí pèpéle onígi tí wọ́n ṣe fún àpéjọ náà; àwọn tó dúró sápá ọ̀tún rẹ̀ ni Matitáyà, Ṣímà, Ánáyà, Ùráyà, Hilikáyà àti Maaseáyà; àwọn tó sì wà lápá òsì rẹ̀ ni Pedáyà, Míṣáẹ́lì, Málíkíjà,+ Háṣúmù, Haṣi-bádánà, Sekaráyà àti Méṣúlámù.

5 Ẹ́sírà ṣí ìwé náà lójú gbogbo èèyàn, nítorí ó yọ sókè ju gbogbo wọn lọ. Bí ó sì ṣe ṣí i, gbogbo àwọn èèyàn náà dìde. 6 Nígbà náà, Ẹ́sírà yin Jèhófà Ọlọ́run tòótọ́, Ẹni ńlá, gbogbo àwọn èèyàn náà sọ pé, “Àmín!* Àmín!”+ wọ́n sì gbé ọwọ́ wọn sókè. Wọ́n tẹrí ba, wọ́n wólẹ̀, wọ́n sì dojú bolẹ̀ fún Jèhófà. 7 Jéṣúà, Bánì, Ṣerebáyà,+ Jámínì, Ákúbù, Ṣábétáì, Hodáyà, Maaseáyà, Kélítà, Asaráyà, Jósábádì,+ Hánánì àti Pẹláyà, tí wọ́n jẹ́ ọmọ Léfì, ń ṣàlàyé Òfin náà fún àwọn èèyàn náà,+ orí ìdúró sì ni àwọn èèyàn náà wà. 8 Wọ́n ń ka ìwé náà sókè nìṣó látinú Òfin Ọlọ́run tòótọ́, wọ́n ń ṣàlàyé rẹ̀ lọ́nà tó ṣe kedere, wọ́n sì ń túmọ̀ rẹ̀; torí náà, wọ́n jẹ́ kí àwọn èèyàn náà lóye ohun tí wọ́n kà.+

9 Nehemáyà tó jẹ́ gómìnà* nígbà yẹn, Ẹ́sírà + tó jẹ́ àlùfáà àti adàwékọ* pẹ̀lú àwọn ọmọ Léfì tí wọ́n ń kọ́ àwọn èèyàn sọ fún gbogbo àwọn èèyàn náà pé: “Ọjọ́ yìí jẹ́ mímọ́ lójú Jèhófà Ọlọ́run yín.+ Ẹ má ṣọ̀fọ̀, ẹ má sì sunkún.” Nítorí gbogbo àwọn èèyàn náà ń sunkún bí wọ́n ṣe gbọ́ ọ̀rọ̀ inú Òfin náà. 10 Ó sọ fún wọn pé: “Ẹ lọ, ẹ jẹ àwọn ohun tó dọ́ṣọ̀,* ẹ mu àwọn ohun dídùn, kí ẹ sì fi oúnjẹ ránṣẹ́+ sí àwọn tí kò ní nǹkan kan; nítorí ọjọ́ yìí jẹ́ mímọ́ lójú Olúwa wa, ẹ má sì banú jẹ́, nítorí ìdùnnú Jèhófà ni ibi ààbò* yín.” 11 Àwọn ọmọ Léfì sì ń fi gbogbo àwọn èèyàn náà lọ́kàn balẹ̀ pé: “Ẹ dákẹ́! nítorí ọjọ́ yìí jẹ́ mímọ́; ẹ má sì banú jẹ́.” 12 Torí náà, gbogbo àwọn èèyàn náà lọ, wọ́n jẹ, wọ́n sì mu, wọ́n fi oúnjẹ ránṣẹ́ sí àwọn míì, inú wọn sì ń dùn gan-an,+ nítorí ọ̀rọ̀ tí wọ́n gbọ́ yé wọn.+

13 Ní ọjọ́ kejì, àwọn olórí agbo ilé gbogbo àwọn èèyàn náà, àwọn àlùfáà àti àwọn ọmọ Léfì kóra jọ sọ́dọ̀ Ẹ́sírà adàwékọ,* kí wọ́n lè túbọ̀ lóye àwọn ọ̀rọ̀ inú Òfin náà. 14 Wọ́n wá rí i nínú Òfin pé Jèhófà pàṣẹ nípasẹ̀ Mósè pé inú àtíbàbà ni kí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì máa gbé nígbà àjọyọ̀ ní oṣù keje+ 15 àti pé kí wọ́n polongo,+ kí wọ́n sì kéde káàkiri gbogbo ìlú wọn àti ní gbogbo Jerúsálẹ́mù pé: “Ẹ lọ sí àwọn agbègbè olókè, kí ẹ sì mú ẹ̀ka eléwé igi ólífì, ti igi ahóyaya, ti igi mátílì àti imọ̀ ọ̀pẹ pẹ̀lú ẹ̀ka àwọn igi míì tó léwé dáadáa wá láti fi wọ́n ṣe àtíbàbà, gẹ́gẹ́ bó ṣe wà lákọsílẹ̀.”

16 Ni àwọn èèyàn náà bá jáde lọ, wọ́n sì kó wọn wá láti fi wọ́n ṣe àtíbàbà fún ara wọn, kálukú sórí òrùlé rẹ̀ àti sí àgbàlá wọn àti àgbàlá ilé Ọlọ́run tòótọ́,+ bákan náà, wọ́n ṣe é sí gbàgede ìlú ní Ẹnubodè Omi+ àti gbàgede ìlú tó wà ní Ẹnubodè Éfúrémù.+ 17 Bí gbogbo àwùjọ* àwọn tó dé láti ìgbèkùn ṣe ṣe àwọn àtíbàbà nìyẹn, wọ́n sì ń gbé inú àwọn àtíbàbà náà, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kò tíì ṣe é báyìí rí láti ìgbà ayé Jóṣúà+ ọmọ Núnì títí di ọjọ́ yẹn, ìdí nìyẹn tí ìdùnnú fi ṣubú layọ̀ láàárín wọn.+ 18 Ojoojúmọ́ ni wọ́n ń ka ìwé Òfin Ọlọ́run tòótọ́,+ láti ọjọ́ àkọ́kọ́ títí di ọjọ́ tó kẹ́yìn. Wọ́n sì fi ọjọ́ méje ṣe àjọyọ̀ náà, ní ọjọ́ kẹjọ, wọ́n ṣe àpéjọ ọlọ́wọ̀, gẹ́gẹ́ bí òfin ṣe sọ.+

9 Ní ọjọ́ kẹrìnlélógún oṣù yìí, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kóra jọ; wọ́n gbààwẹ̀, wọ́n wọ aṣọ ọ̀fọ̀,* wọ́n sì da iyẹ̀pẹ̀ sórí.+ 2 Àwọn àtọmọdọ́mọ Ísírẹ́lì wá ya ara wọn sọ́tọ̀ kúrò lára gbogbo àwọn àjèjì,+ wọ́n dìde dúró, wọ́n sì jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ wọn àti àṣìṣe àwọn bàbá wọn.+ 3 Lẹ́yìn náà, wọ́n dìde dúró ní àyè wọn, wọ́n sì fi wákàtí mẹ́ta* ka ìwé Òfin+ Jèhófà Ọlọ́run wọn sókè; wọ́n fi wákàtí mẹ́ta míì jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ wọn, wọ́n sì ń wólẹ̀ fún Jèhófà Ọlọ́run wọn.

4 Jéṣúà, Bánì, Kádímíélì, Ṣebanáyà, Búnì, Ṣerebáyà,+ Bánì àti Kénánì dúró lórí pèpéle+ àwọn ọmọ Léfì, wọ́n gbé ohùn wọn sókè, wọ́n sì ń sunkún sí Jèhófà Ọlọ́run wọn. 5 Àwọn ọmọ Léfì, ìyẹn Jéṣúà, Kádímíélì, Bánì, Haṣabanéáyà, Ṣerebáyà, Hodáyà, Ṣebanáyà àti Petaháyà sọ pé: “Ẹ dìde, kí ẹ yin Jèhófà Ọlọ́run yín títí láé àti láéláé.*+ Kí wọ́n yin orúkọ rẹ ológo, èyí tí a gbé ga ju gbogbo ìbùkún àti ìyìn lọ.

6 “Ìwọ nìkan ṣoṣo ni Jèhófà;+ ìwọ lo dá ọ̀run, àní ọ̀run àwọn ọ̀run àti gbogbo ọmọ ogun wọn, ayé àti gbogbo ohun tó wà lórí rẹ̀, àwọn òkun àti gbogbo ohun tó wà nínú wọn. O pa gbogbo wọn mọ́, àwọn ọmọ ogun ọ̀run sì ń forí balẹ̀ fún ọ. 7 Ìwọ ni Jèhófà Ọlọ́run tòótọ́, tó yan Ábúrámù,+ tó mú un jáde kúrò ní Úrì,+ ìlú àwọn ará Kálídíà, tó sì sọ orúkọ rẹ̀ ní Ábúráhámù.+ 8 O rí i pé ó jẹ́ olóòótọ́ níwájú rẹ,+ torí náà, o bá a dá májẹ̀mú láti fún un ní ilẹ̀ àwọn ọmọ Kénáánì, àwọn ọmọ Hétì, àwọn Ámórì, àwọn Pérísì, àwọn ará Jébúsì àti àwọn Gẹ́gáṣì, pé kó fún àwọn ọmọ* rẹ̀;+ o sì mú ìlérí rẹ ṣẹ nítorí pé olódodo ni ọ́.

9 “O rí ìpọ́njú àwọn baba ńlá wa ní Íjíbítì,+ o sì gbọ́ igbe ẹkún wọn ní Òkun Pupa. 10 O wá ṣe àwọn iṣẹ́ àmì àti àwọn iṣẹ́ ìyanu láti fìyà jẹ Fáráò àti gbogbo àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pẹ̀lú gbogbo àwọn èèyàn ilẹ̀ rẹ̀,+ torí o mọ̀ pé wọ́n ti kọjá àyè wọn+ sí àwọn èèyàn rẹ. O ṣe orúkọ fún ara rẹ, orúkọ náà sì wà títí dòní.+ 11 O pín òkun sí méjì níwájú wọn, kí wọ́n lè gba àárín òkun kọjá lórí ilẹ̀ gbígbẹ,+ o fi àwọn tó ń lépa wọn sọ̀kò sínú ibú bí òkúta tí a jù sínú omi tó ń ru gùdù.+ 12 O fi ọwọ̀n ìkùukùu* darí wọn ní ọ̀sán, o sì fi ọwọ̀n iná* darí wọn ní òru, láti fún wọn ní ìmọ́lẹ̀ ní ọ̀nà tí wọ́n máa gbà.+ 13 O sọ̀ kalẹ̀ sórí Òkè Sínáì,+ o bá wọn sọ̀rọ̀ láti ọ̀run,+ o sì fún wọn ní àwọn ìdájọ́ òdodo, àwọn òfin òtítọ́,* àwọn ìlànà àti àwọn àṣẹ tó dáa.+ 14 O jẹ́ kí wọ́n mọ Sábáàtì mímọ́+ rẹ, o sì fún wọn ní àṣẹ, ìlànà àti òfin nípasẹ̀ Mósè ìránṣẹ́ rẹ. 15 O fún wọn ní oúnjẹ láti ọ̀run nígbà tí ebi ń pa wọ́n,+ o fún wọn ní omi látinú àpáta nígbà tí òùngbẹ ń gbẹ wọ́n,+ o sì ní kí wọ́n wọ ilẹ̀ tí o búra* pé wàá fún wọn, kí wọ́n sì gbà á.

16 “Àmọ́, àwọn baba ńlá wa kọjá àyè wọn,+ wọ́n sì ya alágídí,*+ wọn kò fetí sí àwọn àṣẹ rẹ. 17 Wọn ò fetí sílẹ̀,+ wọn ò sì rántí àwọn ohun àgbàyanu tí o ṣe láàárín wọn, àmọ́ wọ́n ya alágídí,* wọ́n sì yan olórí láti kó wọn pa dà sí ipò ẹrú wọn ní Íjíbítì.+ Ṣùgbọ́n Ọlọ́run tó ṣe tán láti dárí jini* ni ọ́, o jẹ́ ẹni tó ń gba tẹni rò* àti aláàánú, o kì í tètè bínú, ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀* sì pọ̀ gidigidi,+ o ò pa wọ́n tì.+ 18 Kódà nígbà tí wọ́n ṣe ère onírin* ọmọ màlúù fún ara wọn, tí wọ́n sì ń sọ pé, ‘Ọlọ́run rẹ nìyí tó mú ọ jáde kúrò ní Íjíbítì,’+ tí wọ́n hu ìwà àìlọ́wọ̀ tó bùáyà, 19 síbẹ̀ ìwọ, nínú àánú ńlá rẹ, o ò kọ̀ wọ́n sílẹ̀ nínú aginjù.+ Ọwọ̀n ìkùukùu* kò kúrò lórí wọn ní ọ̀sán láti máa darí wọn ní ọ̀nà wọn, ọwọ̀n iná* kò sì kúrò ní òru láti fún wọn ní ìmọ́lẹ̀ ní ọ̀nà tí wọ́n máa gbà.+ 20 O fún wọn ní ẹ̀mí rere rẹ láti jẹ́ kí wọ́n ní ìjìnlẹ̀ òye,+ o ò fawọ́ mánà rẹ sẹ́yìn kúrò ní ẹnu wọn,+ o sì fún wọn ní omi nígbà tí òùngbẹ ń gbẹ wọ́n.+ 21 Ogójì (40) ọdún lo fi pèsè oúnjẹ fún wọn ní aginjù.+ Wọn ò ṣaláìní nǹkan kan. Aṣọ wọn ò gbó,+ ẹsẹ̀ wọn ò sì wú.

22 “O fún wọn ní àwọn ìjọba àti àwọn èèyàn, o sì pín wọn ní ẹyọ-ẹyọ fún wọn,+ kí wọ́n lè gba ilẹ̀ Síhónì,+ ìyẹn ilẹ̀ ọba Hẹ́ṣíbónì+ àti ilẹ̀ Ógù+ ọba Báṣánì. 23 O mú kí àwọn ọmọ wọn pọ̀ bí ìràwọ̀ ojú ọ̀run.+ Lẹ́yìn náà, o mú wọn wá sí ilẹ̀ tí o ṣèlérí fún àwọn baba ńlá wọn pé kí wọ́n wọ̀, kí wọ́n sì gbà.+ 24 Torí náà, àwọn ọmọ wọn wọlé, wọ́n sì gba ilẹ̀ náà,+ o ṣẹ́gun àwọn ọmọ Kénáánì tó ń gbé ilẹ̀ náà níwájú wọn,+ o sì fi wọ́n lé wọn lọ́wọ́, látorí àwọn ọba wọn dórí àwọn èèyàn ilẹ̀ náà, kí wọ́n lè ṣe wọ́n bí wọ́n ṣe fẹ́. 25 Wọ́n gba àwọn ìlú olódi+ àti ilẹ̀ ọlọ́ràá,*+ wọ́n gba àwọn ilé tí oríṣiríṣi ohun rere kún inú rẹ̀, wọ́n gba àwọn kòtò omi tí wọ́n ti gbẹ́ síbẹ̀, àwọn ọgbà àjàrà, àwọn oko ólífì+ àti àwọn igi eléso tó pọ̀ rẹpẹtẹ. Torí náà, wọ́n jẹ, wọ́n yó, wọ́n sì sanra, wọ́n gbádùn oore ńlá rẹ.

26 “Àmọ́, wọ́n ya aláìgbọràn, wọ́n ṣọ̀tẹ̀ sí ọ,+ wọ́n sì kẹ̀yìn sí Òfin rẹ.* Wọ́n pa àwọn wòlíì rẹ tó kìlọ̀ fún wọn láti mú wọn pa dà sọ́dọ̀ rẹ, wọ́n sì hu ìwà àìlọ́wọ̀ tó bùáyà.+ 27 Nítorí èyí, o fi wọ́n lé ọwọ́ àwọn ọ̀tá wọn,+ wọ́n sì ń kó wàhálà bá wọn.+ Àmọ́, wọ́n á ké pè ọ́ ní àkókò wàhálà wọn, ìwọ náà á sì gbọ́ láti ọ̀run; nítorí àánú ńlá rẹ, wàá fún wọn ní olùgbàlà láti gbà wọ́n lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá wọn.+

28 “Àmọ́, nígbà tí ara bá ti tù wọ́n, wọ́n á tún ṣe ohun tó burú níwájú rẹ,+ wàá sì fi wọ́n sílẹ̀ sọ́wọ́ àwọn ọ̀tá wọn, wọ́n á sì jọba lé wọn lórí.*+ Lẹ́yìn náà, wọ́n á pa dà, wọ́n á sì ké pè ọ́ pé kí o ran àwọn lọ́wọ́,+ wàá gbọ́ láti ọ̀run, léraléra lo sì ń gbà wọ́n nítorí àánú ńlá rẹ.+ 29 O máa ń kìlọ̀ fún wọn kí o lè mú wọn pa dà wá sínú Òfin rẹ, síbẹ̀ ṣe ni wọ́n ń kọjá àyè wọn, wọn ò sì fetí sí àwọn àṣẹ rẹ;+ wọ́n ń ṣe ohun tó ta ko ìlànà rẹ, èyí tó máa jẹ́ kẹ́ni tó ba ń pa á mọ́ lè wà láàyè.+ Agídí wọn mú kí wọ́n kẹ̀yìn sí ọ, wọ́n mú kí ọrùn wọn le, wọn ò sì fetí sílẹ̀. 30 Ọ̀pọ̀ ọdún lo fi mú sùúrù fún wọn,+ o sì ń fi ẹ̀mí rẹ kìlọ̀ fún wọn nípasẹ̀ àwọn wòlíì rẹ, àmọ́ wọn ò gbọ́. Níkẹyìn, o fi wọ́n lé àwọn èèyàn ilẹ̀ tó yí wọn ká lọ́wọ́.+ 31 Nínú àánú ńlá rẹ, o ò pa wọ́n run,+ o ò sì fi wọ́n sílẹ̀, nítorí Ọlọ́run tó ń gba tẹni rò* àti aláàánú ni ọ́.+

32 “Ní báyìí, ìwọ Ọlọ́run wa, Ọlọ́run títóbi, alágbára ńlá, tó sì yẹ lẹ́ni tí à ń bẹ̀rù, tó ń pa májẹ̀mú rẹ̀ mọ́, tí ó sì ń fi ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ hàn,+ má fojú kékeré wo gbogbo ìnira tó bá àwa, àwọn ọba wa, àwọn ìjòyè wa,+ àwọn àlùfáà wa,+ àwọn wòlíì wa,+ àwọn baba ńlá wa àti gbogbo àwọn èèyàn rẹ láti ìgbà àwọn ọba Ásíríà+ títí di òní yìí. 33 O ò lẹ́bi kankan nínú gbogbo ohun tó dé bá wa, nítorí òótọ́ lo fi bá wa lò; àwa la hùwà burúkú.+ 34 Ní ti àwọn ọba wa, àwọn ìjòyè wa, àwọn àlùfáà wa àti àwọn baba ńlá wa, wọn ò pa Òfin rẹ mọ́, wọn ò sì fiyè sí àwọn àṣẹ rẹ tàbí àwọn ìránnilétí* rẹ tí o fi kìlọ̀ fún wọn. 35 Kódà nígbà tí wọ́n wà lábẹ́ ìjọba ti ara wọn, tí wọ́n sì ń gbádùn ọ̀pọ̀ ohun rere tí o fún wọn, tí wọ́n ń gbé lórí ilẹ̀ tó fẹ̀, tó sì lọ́ràá* tí o fi jíǹkí wọn, wọn ò sìn ọ́,+ wọn ò sì jáwọ́ nínú ìwà búburú tí wọ́n ń hù. 36 Àwa rèé lónìí, àwa ẹrú,+ bẹ́ẹ̀ ni, ẹrú lórí ilẹ̀ tí o fún àwọn baba ńlá wa pé kí wọ́n máa jẹ èso rẹ̀ àti ohun rere rẹ̀. 37 Ọ̀pọ̀ àwọn ohun rere tí ilẹ̀ náà ń mú jáde jẹ́ ti àwọn ọba tí o fi ṣe olórí wa nítorí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa.+ Wọ́n ń ṣàkóso àwa* àti àwọn ẹran ọ̀sìn wa bó ṣe wù wọ́n, a sì wà nínú wàhálà ńlá.

38 “Pẹ̀lú gbogbo èyí, a wọnú àdéhùn kan, a sì kọ àdéhùn+ náà sílẹ̀, àwọn ìjòyè wa, àwọn ọmọ Léfì wa àti àwọn àlùfáà wa ti fọwọ́ sí i, wọ́n sì gbé èdìdì lé e.”+

10 Àwọn tó fọwọ́ sí i, tí wọ́n sì gbé èdìdì wọn lé e+ ni:

Nehemáyà, tó jẹ́ gómìnà,* ọmọ Hakaláyà

Àti Sedekáyà, 2 Seráyà, Asaráyà, Jeremáyà, 3 Páṣúrì, Amaráyà, Málíkíjà, 4 Hátúṣì, Ṣebanáyà, Málúkù, 5 Hárímù,+ Mérémótì, Ọbadáyà, 6 Dáníẹ́lì,+ Gínétónì, Bárúkù, 7 Méṣúlámù, Ábíjà, Míjámínì, 8 Maasáyà, Bílígáì àti Ṣemáyà; àwọn yìí jẹ́ àlùfáà.

9 Àwọn ọmọ Léfì tó fọwọ́ sí i ni: Jéṣúà ọmọ Asanáyà, Bínúì látinú àwọn ọmọ Hénádádì, Kádímíélì+ 10 àti arákùnrin wọn Ṣebanáyà, Hodáyà, Kélítà, Pẹláyà, Hánánì, 11 Máíkà, Réhóbù, Haṣabáyà, 12 Sákúrì, Ṣerebáyà,+ Ṣebanáyà, 13 Hodáyà, Bánì àti Bẹnínù.

14 Àwọn olórí àwọn èèyàn náà tó fọwọ́ sí i ni: Páróṣì, Pahati-móábù,+ Élámù, Sátù, Bánì, 15 Búnì, Ásígádì, Bébáì, 16 Ádóníjà, Bígífáì, Ádínì, 17 Átérì, Hẹsikáyà, Ásúrì, 18 Hodáyà, Háṣúmù, Bísáì, 19 Hárífù, Ánátótì, Nébáì, 20 Mágípíáṣì, Méṣúlámù, Hésírì, 21 Meṣesábélì, Sádókù, Jádúà, 22 Pẹlatáyà, Hánánì, Ánáyà, 23 Hóṣéà, Hananáyà, Háṣúbù, 24 Hálóhéṣì, Pílíhà, Ṣóbékì, 25 Réhúmù, Háṣábínà, Maaseáyà, 26 Áhíjà, Hánánì, Ánánì, 27 Málúkù, Hárímù àti Báánà.

28 Ìyókù àwọn èèyàn náà, ìyẹn àwọn àlùfáà, àwọn ọmọ Léfì, àwọn aṣọ́bodè, àwọn akọrin, àwọn ìránṣẹ́ tẹ́ńpìlì* àti gbogbo àwọn tó ya ara wọn sọ́tọ̀ kúrò lára àwọn èèyàn ilẹ̀ tó yí wọn ká kí wọ́n lè pa Òfin Ọlọ́run tòótọ́ mọ́,+ pẹ̀lú àwọn ìyàwó wọn, àwọn ọmọkùnrin wọn àti àwọn ọmọbìnrin wọn, gbogbo àwọn tó ní ìmọ̀ àti òye,* 29 dara pọ̀ mọ́ àwọn arákùnrin wọn, àwọn olókìkí àárín wọn, wọ́n gégùn-ún, wọ́n sì búra pé wọ́n á máa rìn nínú Òfin Ọlọ́run tòótọ́, èyí tó wá nípasẹ̀ Mósè ìránṣẹ́ Ọlọ́run tòótọ́ àti pé àwọn á rí i pé àwọn ń pa gbogbo àṣẹ Jèhófà Olúwa wa mọ́ àti àwọn ìdájọ́ rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ìlànà rẹ̀. 30 A kò ní fi àwọn ọmọbìnrin wa fún àwọn èèyàn ilẹ̀ náà, a kò sì ní fẹ́ àwọn ọmọbìnrin wọn fún àwọn ọmọkùnrin wa.+

31 Tí àwọn èèyàn ilẹ̀ náà bá kó ọjà tàbí oríṣiríṣi ọkà wá ní ọjọ́ Sábáàtì, a kò ní ra ohunkóhun lọ́wọ́ wọn ní Sábáàtì+ tàbí ní ọjọ́ mímọ́.+ A tún máa fi irè oko wa tó bá jáde ní ọdún keje+ sílẹ̀ àti gbogbo gbèsè tí ẹnikẹ́ni bá jẹ wá.+

32 Bákan náà, a gbé àṣẹ kan kalẹ̀ fún ara wa lẹ́nì kọ̀ọ̀kan pé, a ó máa mú ìdá mẹ́ta ṣékélì* wá lọ́dọọdún fún iṣẹ́ ìsìn ilé* Ọlọ́run wa,+ 33 fún búrẹ́dì onípele,*+ ọrẹ ọkà ìgbà gbogbo,+ ẹbọ sísun ìgbà gbogbo ti Sábáàtì+ pẹ̀lú ti òṣùpá tuntun+ àti fún àwọn àsè tí a yàn,+ àwọn ohun mímọ́ àti ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀+ láti ṣe ètùtù fún Ísírẹ́lì àti fún gbogbo iṣẹ́ ilé Ọlọ́run wa.

34 A tún ṣẹ́ kèké lórí bí àwọn àlùfáà, àwọn ọmọ Léfì àti àwọn èèyàn náà á ṣe máa mú igi wá sí ilé Ọlọ́run wa, ní agboolé-agboolé àwọn bàbá wa, ní àkókò tí a yàn lọ́dọọdún, láti máa fi dáná lórí pẹpẹ Jèhófà Ọlọ́run wa, bó ṣe wà lákọsílẹ̀ nínú Òfin.+ 35 A ó tún máa mú àkọ́so èso ilẹ̀ wa àti àkọ́so èso oríṣiríṣi igi wá lọ́dọọdún sí ilé Jèhófà+ 36 àti àkọ́bí àwọn ọmọkùnrin wa àti ti ẹran ọ̀sìn wa+ pẹ̀lú àkọ́bí ọ̀wọ́ ẹran wa àti ti agbo ẹran wa bó ṣe wà lákọsílẹ̀ nínú Òfin. A ó mú wọn wá sí ilé Ọlọ́run wa, sọ́dọ̀ àwọn àlùfáà tó ń ṣiṣẹ́ nínú ilé Ọlọ́run wa.+ 37 Bákan náà, a ó máa mú àkọ́so ọkà tí a kò lọ̀ kúnná+ wá àti àwọn ọrẹ pẹ̀lú èso oríṣiríṣi igi+ àti wáìnì tuntun pẹ̀lú òróró,+ a ó sì kó wọn wá fún àwọn àlùfáà ní àwọn yàrá tí wọ́n ń kó nǹkan pa mọ́ sí* ní ilé Ọlọ́run wa,+ a ó sì kó ìdá mẹ́wàá irè oko ilẹ̀ wa fún àwọn ọmọ Léfì,+ torí àwọn ni wọ́n ń gba ìdá mẹ́wàá ní gbogbo ìlú tí a ti ń ṣiṣẹ́ àgbẹ̀.

38 Kí àlùfáà, ọmọ Áárónì, wà pẹ̀lú àwọn ọmọ Léfì nígbà tí àwọn ọmọ Léfì bá ń gba ìdá mẹ́wàá; kí àwọn ọmọ Léfì mú ìdá mẹ́wàá lára ìdá mẹ́wàá ti ilé Ọlọ́run wa,+ kí wọ́n sì kó o sí àwọn yàrá* tó wà ní ilé ìkẹ́rùsí. 39 Inú àwọn yàrá tí wọ́n ń kó nǹkan pa mọ́ sí* ni kí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì àti àwọn ọmọ Léfì máa mú ọrẹ+ ọkà, wáìnì tuntun àti òróró wá,+ ibẹ̀ sì ni kí àwọn nǹkan èlò ibi mímọ́ máa wà títí kan àwọn àlùfáà tó ń ṣiṣẹ́ ìsìn àti àwọn aṣọ́bodè pẹ̀lú àwọn akọrin. A kò sì ní pa ilé Ọlọ́run wa tì.+

11 Àwọn olórí àwọn èèyàn náà ń gbé ní Jerúsálẹ́mù;+ àmọ́ ìyókù àwọn èèyàn náà ṣẹ́ kèké+ láti mú ẹnì kan nínú èèyàn mẹ́wàá láti lọ máa gbé ní Jerúsálẹ́mù, ìlú mímọ́, nígbà tí àwọn mẹ́sàn-án yòókù á máa gbé ní àwọn ìlú míì. 2 Àwọn èèyàn náà sì súre fún gbogbo àwọn ọkùnrin tó yọ̀ǹda ara wọn láti lọ máa gbé ní Jerúsálẹ́mù.

3 Àwọn tó tẹ̀ lé e yìí ni àwọn olórí ìpínlẹ̀* tí wọ́n ń gbé ní Jerúsálẹ́mù. (Ìyókù àwọn tó wà ní Ísírẹ́lì, àwọn àlùfáà, àwọn ọmọ Léfì, àwọn ìránṣẹ́ tẹ́ńpìlì*+ àti àwọn ọmọ àwọn ìránṣẹ́ Sólómọ́nì,+ wọ́n ń gbé ní àwọn ìlú míì ní Júdà, kálukú sì ń gbé lórí ohun ìní rẹ̀ nínú ìlú rẹ̀.+

4 Àwọn míì tó tún ń gbé ní Jerúsálẹ́mù ni àwọn kan lára àwọn èèyàn Júdà àti Bẹ́ńjámínì.) Lára àwọn èèyàn Júdà ni Átáyà ọmọ Ùsáyà ọmọ Sekaráyà ọmọ Amaráyà ọmọ Ṣẹfatáyà ọmọ Máhálálélì látinú àwọn ọmọ Pérésì+ 5 àti Maaseáyà ọmọ Bárúkù ọmọ Kólíhósè ọmọ Hasáyà ọmọ Ádáyà ọmọ Jóyáríbù ọmọ Sekaráyà látinú ìdílé àwọn ọmọ Ṣélà. 6 Gbogbo àwọn ọmọ Pérésì tó ń gbé ní Jerúsálẹ́mù jẹ́ ọgọ́rùn-ún mẹ́rin ó lé méjìdínláàádọ́rin (468) ọkùnrin tó dáńgájíá.

7 Àwọn èèyàn Bẹ́ńjámínì nìyí: Sáálù+ ọmọ Méṣúlámù ọmọ Jóédì ọmọ Pedáyà ọmọ Koláyà ọmọ Maaseáyà ọmọ Ítíélì ọmọ Jeṣáyà, 8 àwọn tó tẹ̀ lé e ni Gábáì àti Sáláì, wọ́n jẹ́ ọgọ́rùn-ún mẹ́sàn-án ó lé méjìdínlọ́gbọ̀n (928); 9 Jóẹ́lì ọmọ Síkírì ni alábòójútó wọn, Júdà ọmọ Hásénúà sì ni igbá kejì rẹ̀ ní ìlú náà.

10 Látinú àwọn àlùfáà: Jedáyà ọmọ Jóyáríbù, Jákínì,+ 11 Seráyà ọmọ Hilikáyà ọmọ Méṣúlámù ọmọ Sádókù ọmọ Méráótì ọmọ Áhítúbù,+ aṣáájú ní ilé* Ọlọ́run tòótọ́ 12 àti àwọn arákùnrin wọn tó ń ṣiṣẹ́ ìsìn ní tẹ́ńpìlì, wọ́n jẹ́ ọgọ́rùn-ún mẹ́jọ ó lé méjìlélógún (822) àti Ádáyà ọmọ Jéróhámù ọmọ Pẹlaláyà ọmọ Ámísì ọmọ Sekaráyà ọmọ Páṣúrì+ ọmọ Málíkíjà 13 àti àwọn arákùnrin rẹ̀, àwọn olórí agbo ilé, iye wọn jẹ́ igba ó lé méjìlélógójì (242) àti Ámáṣísáì ọmọ Ásárẹ́lì ọmọ Ásáì ọmọ Méṣílémótì ọmọ Ímérì 14 àti àwọn arákùnrin wọn tí wọ́n lágbára tí wọ́n sì nígboyà, wọ́n jẹ́ méjìdínláàádóje (128), alábòójútó wọn ni Sábídíẹ́lì, ó wá láti ìdílé kan tó lókìkí.

15 Látinú àwọn ọmọ Léfì: Ṣemáyà+ ọmọ Háṣúbù, ọmọ Ásíríkámù ọmọ Haṣabáyà ọmọ Búnì 16 àti Ṣábétáì+ àti Jósábádì,+ látinú àwọn olórí àwọn ọmọ Léfì, tí wọ́n ń bójú tó àwọn iṣẹ́ míì tó jẹ mọ́ ilé Ọlọ́run tòótọ́ 17 àti Matanáyà,+ ọmọ Míkà ọmọ Sábídì ọmọ Ásáfù,+ olùdarí orin, tó máa ń gbé orin ìyìn nígbà àdúrà+ àti Bakibúkáyà tó jẹ́ èkejì nínú àwọn arákùnrin rẹ̀ pẹ̀lú Ábídà ọmọ Ṣámúà ọmọ Gálálì ọmọ Jédútúnì.+ 18 Gbogbo àwọn ọmọ Léfì tó wà nínú ìlú mímọ́ náà jẹ́ igba ó lé mẹ́rìnlélọ́gọ́rin (284).

19 Àwọn aṣọ́bodè ni Ákúbù, Tálímónì+ àti àwọn arákùnrin wọn tó ń ṣọ́ àwọn ẹnubodè, wọ́n jẹ́ méjìléláàádọ́sàn-án (172).

20 Ìyókù àwọn tó wà ní Ísírẹ́lì àti àwọn àlùfáà pẹ̀lú àwọn ọmọ Léfì sì wà nínú gbogbo àwọn ìlú míì ní Júdà, kálukú lórí ilẹ̀ tó jogún.* 21 Àwọn ìránṣẹ́ tẹ́ńpìlì*+ ń gbé ní Ófélì.+ Síhà àti Gíṣípà ló sì ń bójú tó àwọn ìránṣẹ́ tẹ́ńpìlì.*

22 Alábòójútó àwọn ọmọ Léfì ní Jerúsálẹ́mù ni Úsáì ọmọ Bánì ọmọ Haṣabáyà ọmọ Matanáyà+ ọmọ Máíkà látinú àwọn ọmọ Ásáfù, àwọn akọrin; òun ló sì ń bójú tó iṣẹ́ ilé Ọlọ́run tòótọ́. 23 Ọba pàṣẹ kan nítorí wọn,+ ètò sì wà fún ohun tí wọ́n gbọ́dọ̀ máa fún àwọn akọrin bí ọjọ́ kọ̀ọ̀kan ṣe gbà. 24 Petaháyà ọmọ Meṣesábélì látinú àwọn ọmọ Síírà ọmọ Júdà sì ni agbani-nímọ̀ràn ọba* nínú gbogbo ọ̀ràn àwọn èèyàn náà.

25 Ní ti àwọn ibi tí wọ́n tẹ̀ dó sí pẹ̀lú àwọn pápá wọn, àwọn kan lára àwọn èèyàn Júdà ń gbé ní Kiriati-ábà+ àti àwọn àrọko rẹ̀,* ní Díbónì àti àwọn àrọko rẹ̀, ní Jekabúsélì+ àti àwọn ìgbèríko rẹ̀, 26 ní Jéṣúà, ní Móládà,+ ní Bẹti-pélétì,+ 27 ní Hasari-ṣúálì,+ ní Bíá-ṣébà àti àwọn àrọko rẹ̀,* 28 ní Síkílágì,+ ní Mékónà àti àwọn àrọko rẹ̀,* 29 ní Ẹ́ń-rímónì,+ ní Sórà+ àti ní Jámútì, 30 ní Sánóà,+ ní Ádúlámù àti àwọn ìgbèríko wọn, ní Lákíṣì+ àti àwọn pápá rẹ̀ àti ní Ásékà+ àti àwọn àrọko* rẹ̀. Wọ́n ń gbé láti* Bíá-ṣébà títí lọ dé Àfonífojì Hínómù.+

31 Àwọn èèyàn Bẹ́ńjámínì sì wà ní Gébà,+ Míkímáṣì, Áíjà, Bẹ́tẹ́lì+ àti àwọn àrọko* rẹ̀, 32 Ánátótì,+ Nóbù,+ Ananíà, 33 Hásórì, Rámà,+ Gítáímù, 34 Hádídì, Sébóímù, Nébálátì, 35 Lódì àti Ónò,+ àfonífojì àwọn oníṣẹ́ ọnà. 36 Wọ́n sì pín lára àwọn àwùjọ àwọn ọmọ Léfì tó wà ní Júdà sọ́dọ̀ Bẹ́ńjámínì.

12 Àwọn àlùfáà àti àwọn ọmọ Léfì tó tẹ̀ lé Serubábélì+ ọmọ Ṣéálítíẹ́lì+ àti Jéṣúà+ nìyí: Seráyà, Jeremáyà, Ẹ́sírà, 2 Amaráyà, Málúkù, Hátúṣì, 3 Ṣẹkanáyà, Réhúmù, Mérémótì, 4 Ídò, Gínétóì, Ábíjà, 5 Míjámínì, Maadáyà, Bílígà, 6 Ṣemáyà, Jóyáríbù, Jedáyà, 7 Sáálù, Ámókì, Hilikáyà àti Jedáyà. Àwọn ni olórí àwọn àlùfáà àti àwọn arákùnrin wọn nígbà ayé Jéṣúà.

8 Àwọn ọmọ Léfì ni Jéṣúà, Bínúì, Kádímíélì,+ Ṣerebáyà, Júdà àti Matanáyà + tó ń gbé orin ọpẹ́ pẹ̀lú àwọn arákùnrin rẹ̀. 9 Bakibúkáyà àti Únì tí wọ́n jẹ́ arákùnrin wọn sì dúró ní òdìkejì wọn láti máa ṣe iṣẹ́ ẹ̀ṣọ́.* 10 Jéṣúà bí Jóyákímù, Jóyákímù bí Élíáṣíbù,+ Élíáṣíbù sì bí Jóyádà.+ 11 Jóyádà bí Jónátánì, Jónátánì sì bí Jádúà.

12 Nígbà ayé Jóyákímù, àwọn àlùfáà tí wọ́n jẹ́ olórí agbo ilé nìyí: fún Seráyà,+ Meráyà; fún Jeremáyà, Hananáyà; 13 fún Ẹ́sírà,+ Méṣúlámù; fún Amaráyà, Jèhóhánánì; 14 fún Málúkì, Jónátánì; fún Ṣebanáyà, Jósẹ́fù; 15 fún Hárímù,+ Ádúnà; fún Méráótì, Hélíkáì; 16 fún Ídò, Sekaráyà; fún Gínétónì, Méṣúlámù; 17 fún Ábíjà,+ Síkírì; fún Míníámínì, . . . ;* fún Moadáyà, Pílítáì; 18 fún Bílígà,+ Ṣámúà; fún Ṣemáyà, Jèhónátánì; 19 fún Jóyáríbù, Máténáì; fún Jedáyà,+ Úsáì; 20 fún Sáláì, Káláì; fún Ámókì, Ébérì; 21 fún Hilikáyà, Haṣabáyà; fún Jedáyà, Nétánélì.

22 Àwọn olórí agbo ilé àwọn ọmọ Léfì àti ti àwọn àlùfáà wà lákọsílẹ̀ nígbà ayé Élíáṣíbù, Jóyádà, Jóhánánì àti Jádúà,+ títí di ìgbà ìjọba Dáríúsì ará Páṣíà.

23 Àwọn ọmọ Léfì tí wọ́n jẹ́ olórí agbo ilé wà lákọsílẹ̀ nínú ìwé ìtàn àkókò náà, títí di ìgbà ayé Jóhánánì ọmọ Élíáṣíbù. 24 Àwọn olórí àwọn ọmọ Léfì ni Haṣabáyà, Ṣerebáyà àti Jéṣúà+ ọmọ Kádímíélì,+ àwọn arákùnrin wọn dúró ní òdìkejì wọn láti máa yin Ọlọ́run, kí wọ́n sì máa dúpẹ́, gẹ́gẹ́ bí Dáfídì èèyàn Ọlọ́run tòótọ́ ṣe pa á láṣẹ,+ àwùjọ ẹ̀ṣọ́ kan dojú kọ àwùjọ ẹ̀ṣọ́ kejì. 25 Matanáyà,+ Bakibúkáyà, Ọbadáyà, Méṣúlámù, Tálímónì àti Ákúbù+ jẹ́ aṣọ́bodè+ tó ń ṣọ́ àwọn yàrá tí wọ́n ń kó nǹkan pa mọ́ sí lẹ́gbẹ̀ẹ́ ẹnubodè. 26 Àwọn yìí ṣiṣẹ́ nígbà ayé Jóyákímù ọmọ Jéṣúà + ọmọ Jósádákì àti nígbà ayé Nehemáyà gómìnà àti Ẹ́sírà+ tó jẹ́ àlùfáà àti adàwékọ.*

27 Nígbà ayẹyẹ ṣíṣí ògiri Jerúsálẹ́mù, wọ́n wá àwọn ọmọ Léfì, wọ́n sì mú wọn wá sí Jerúsálẹ́mù láti gbogbo ibi tí wọ́n ń gbé kí wọ́n lè ṣe ayẹyẹ náà tayọ̀tayọ̀, pẹ̀lú orin ọpẹ́,+ pẹ̀lú síńbálì* àti àwọn ohun ìkọrin olókùn tín-ín-rín àti háàpù. 28 Àwọn ọmọ àwọn akọrin* kóra jọ láti agbègbè* náà, láti gbogbo àyíká Jerúsálẹ́mù, láti àwọn ibi tí àwọn ará Nétófà+ tẹ̀ dó sí, 29 láti Bẹti-gílígálì+ àti láti àwọn pápá Gébà+ àti Ásímáfẹ́tì,+ nítorí àwọn akọrin ti kọ́ àwọn ibi tí wọ́n á máa gbé ní gbogbo àyíká Jerúsálẹ́mù. 30 Àwọn àlùfáà àti àwọn ọmọ Léfì sọ ara wọn di mímọ́, wọ́n sì sọ àwọn èèyàn náà di mímọ́+ àti àwọn ẹnubodè+ pẹ̀lú ògiri náà.+

31 Lẹ́yìn náà, mo mú àwọn olórí Júdà wá sórí ògiri náà. Yàtọ̀ síyẹn, mo yan ẹgbẹ́ ńlá méjì tó ń kọrin ọpẹ́ àti àwọn àwùjọ tí á máa tẹ̀ lé wọn, ọ̀kan lára àwọn ẹgbẹ́ akọrin náà sì lọ sápá ọ̀tún lórí ògiri tó lọ sí Ẹnubodè Àwọn Òkìtì Eérú.+ 32 Hóṣáyà àti ìdajì àwọn olórí Júdà ń tẹ̀ lé wọn 33 pẹ̀lú Asaráyà, Ẹ́sírà, Méṣúlámù, 34 Júdà, Bẹ́ńjámínì, Ṣemáyà àti Jeremáyà. 35 Lára àwọn ọmọ àlùfáà tó wà pẹ̀lú wọn, tí wọ́n mú kàkàkí+ lọ́wọ́ ni: Sekaráyà ọmọ Jónátánì ọmọ Ṣemáyà ọmọ Matanáyà ọmọ Mikáyà ọmọ Sákúrì ọmọ Ásáfù + 36 àti àwọn arákùnrin rẹ̀, Ṣemáyà àti Ásárẹ́lì, Míláláì, Gíláláì, Máì, Nétánélì, Júdà àti Hánáánì, wọ́n mú ohun ìkọrin Dáfídì+ èèyàn Ọlọ́run tòótọ́ lọ́wọ́; Ẹ́sírà+ adàwékọ* sì ń lọ níwájú wọn. 37 Wọ́n dé Ẹnubodè Ojúsun,+ wọ́n sì lọ tààrà sórí Àtẹ̀gùn+ Ìlú Dáfídì+ níbi ìgòkè ògiri lórí Ilé Dáfídì títí lọ dé Ẹnubodè Omi+ ní ìlà oòrùn.

38 Ẹgbẹ́ akọrin ọpẹ́ kejì gba òdìkejì* lọ, èmi àti ìdajì àwọn èèyàn náà sì tẹ̀ lé wọn, lórí ògiri lókè Ilé Gogoro Ààrò+ títí dé orí Ògiri Fífẹ̀+ 39 àti lókè Ẹnubodè Éfúrémù+ títí dé Ẹnubodè Ìlú Àtijọ́+ àti títí dé Ẹnubodè Ẹja,+ Ilé Gogoro Hánánélì,+ Ilé Gogoro Méà àti títí dé Ẹnubodè Àgùntàn;+ wọ́n sì dúró ní Ẹnubodè Ẹ̀ṣọ́.

40 Nígbà tó yá, ẹgbẹ́ akọrin ọpẹ́ méjèèjì dúró níwájú ilé Ọlọ́run tòótọ́; bẹ́ẹ̀ ni èmi àti ìdajì àwọn alábòójútó tó wà pẹ̀lú mi ṣe 41 àti àwọn àlùfáà, ìyẹn Élíákímù, Maaseáyà, Míníámínì, Mikáyà, Élíóénáì, Sekaráyà àti Hananáyà pẹ̀lú àwọn kàkàkí lọ́wọ́ 42 àti Maaseáyà, Ṣemáyà, Élíásárì, Úsáì, Jèhóhánánì, Málíkíjà, Élámù àti Ésérì. Àwọn akọrin náà kọrin sókè lábẹ́ àbójútó Isiráháyà.

43 Ní ọjọ́ yẹn, wọ́n rú àwọn ẹbọ ńlá, wọ́n sì ń yọ̀,+ nítorí Ọlọ́run tòótọ́ ti mú kí wọ́n yọ ayọ̀ ńlá. Bákan náà, àwọn obìnrin àti àwọn ọmọdé ń yọ̀,+ tó fi jẹ́ pé àwọn tó wà níbi tó jìnnà réré ń gbọ́ ìró ayọ̀ Jerúsálẹ́mù.+

44 Ní ọjọ́ yẹn, wọ́n yan àwọn tí á máa bójú tó àwọn ilé ìkẹ́rùsí,+ èyí tó wà fún àwọn ọrẹ,+ àwọn àkọ́so èso+ àti àwọn ìdá mẹ́wàá.+ Inú àwọn ilé náà ni wọ́n á máa kó àwọn nǹkan tí wọ́n kórè látinú àwọn oko tó wà ní àwọn ìlú sí, gẹ́gẹ́ bí Òfin ṣe sọ+ pé kí wọ́n máa fún àwọn àlùfáà àti àwọn ọmọ Léfì.+ Àwọn èèyàn sì ń yọ̀ ní Júdà torí pé àwọn àlùfáà àti àwọn ọmọ Léfì wà lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn wọn. 45 Wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe iṣẹ́ tí Ọlọ́run yàn fún wọn àti iṣẹ́ ìwẹ̀mọ́, bẹ́ẹ̀ náà ni àwọn akọrin àti àwọn aṣọ́bodè ń ṣe iṣẹ́ tiwọn, gẹ́gẹ́ bí Dáfídì àti Sólómọ́nì ọmọ rẹ̀ ṣe pa á láṣẹ. 46 Nítorí ó ti pẹ́ gan-an láti ìgbà ayé Dáfídì àti Ásáfù tí àwọn olùdarí* ti wà fún àwọn akọrin àti fún àwọn orin ìyìn àti orin ọpẹ́ sí Ọlọ́run.+ 47 Nígbà ayé Serubábélì+ àti nígbà ayé Nehemáyà, gbogbo Ísírẹ́lì ń mú oúnjẹ wá fún àwọn akọrin+ àti àwọn aṣọ́bodè+ bí ọjọ́ kọ̀ọ̀kan bá ṣe gbà. Wọ́n tún ya oúnjẹ sọ́tọ̀ tí wọ́n ń fún àwọn ọmọ Léfì,+ àwọn ọmọ Léfì sì ń ya apá kan sọ́tọ̀ fún àwọn àtọmọdọ́mọ Áárónì.

13 Ní ọjọ́ yẹn, wọ́n ka ìwé Mósè sétí àwọn èèyàn,+ wọ́n sì rí i pé ó wà lákọsílẹ̀ pé àwọn ọmọ Ámónì àti àwọn ọmọ Móábù+ kò gbọ́dọ̀ wá sínú ìjọ Ọlọ́run tòótọ́ láé,+ 2 nítorí wọn kò fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní oúnjẹ àti omi, dípò bẹ́ẹ̀ ṣe ni wọ́n háyà Báláámù láti gégùn-ún fún wọn.+ Àmọ́, Ọlọ́run wa yí ègún náà pa dà sí ìbùkún.+ 3 Nígbà tí wọ́n gbọ́ ọ̀rọ̀ inú Òfin náà, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í ya onírúurú àjèjì* tó wà láàárín Ísírẹ́lì sọ́tọ̀.+

4 Ṣáájú àkókò yìí, Élíáṣíbù + tó jẹ́ ìbátan Tòbáyà+ ni àlùfáà tó ń bójú tó àwọn yàrá tí wọ́n ń kó nǹkan pa mọ́ sí* ní ilé* Ọlọ́run wa.+ 5 Ó ti ṣètò yàrá ńlá kan tí wọ́n ń kó nǹkan pa mọ́ sí* fún un, ibẹ̀ ni wọ́n máa ń kó ọrẹ ọkà sí tẹ́lẹ̀ pẹ̀lú oje igi tùràrí àti àwọn nǹkan èlò, ibẹ̀ tún ni wọ́n ń kó ìdá mẹ́wàá ọkà, ti wáìnì tuntun àti ti òróró+ sí, èyí tó wà fún àwọn ọmọ Léfì,+ àwọn akọrin àti àwọn aṣọ́bodè, ibẹ̀ náà ni wọ́n sì ń kó ọrẹ tó wà fún àwọn àlùfáà sí.+

6 Ní gbogbo àkókò yìí, mi ò sí ní Jerúsálẹ́mù, nítorí mo lọ sọ́dọ̀ ọba ní ọdún kejìlélọ́gbọ̀n+ Atasásítà+ ọba Bábílónì; lẹ́yìn ìgbà yẹn, mo gba àyè kúrò lẹ́nu iṣẹ́ lọ́dọ̀ ọba. 7 Lẹ́yìn náà, mo wá sí Jerúsálẹ́mù, mo sì rí nǹkan burúkú tí Élíáṣíbù+ ṣe nítorí Tòbáyà,+ ó ti ṣètò yàrá kan tí wọ́n ń kó nǹkan pa mọ́ sí fún un ní àgbàlá ilé Ọlọ́run tòótọ́. 8 Nǹkan yìí múnú bí mi gan-an, torí náà, mo da gbogbo ẹrù ilé Tòbáyà sóde yàrá* náà. 9 Lẹ́yìn ìyẹn, mo pàṣẹ, wọ́n sì fọ àwọn yàrá* náà mọ́; mo wá dá àwọn nǹkan èlò ilé Ọlọ́run tòótọ́+ pa dà síbẹ̀ pẹ̀lú ọrẹ ọkà àti oje igi tùràrí.+

10 Mo tún rí i pé wọn ò fún àwọn ọmọ Léfì+ ní ìpín wọn,+ tó fi di pé àwọn ọmọ Léfì àti àwọn akọrin tó ń ṣe iṣẹ́ náà lọ lẹ́nì kọ̀ọ̀kan sí pápá wọn.+ 11 Torí náà, mo bá àwọn alábòójútó wí,+ mo sì sọ pé: “Kí ló dé tí ẹ jẹ́ kí wọ́n pa ilé Ọlọ́run tòótọ́ tì?”+ Ni mo bá kó wọn jọ, mo sì yàn wọ́n pa dà sí ipò wọn. 12 Gbogbo Júdà sì kó ìdá mẹ́wàá+ ọkà àti ti wáìnì tuntun àti ti òróró wá sí àwọn yàrá tí wọ́n ń kó nǹkan pa mọ́ sí.+ 13 Lẹ́yìn náà, mo fi àlùfáà Ṣelemáyà, Sádókù adàwékọ* àti Pedáyà lára àwọn ọmọ Léfì sídìí àbójútó àwọn yàrá tí wọ́n ń kó nǹkan pa mọ́ sí, Hánánì ọmọ Sákúrì ọmọ Matanáyà sì ni olùrànlọ́wọ́ wọn, nítorí wọ́n ṣeé fọkàn tán. Iṣẹ́ wọn ni láti pín nǹkan fún àwọn arákùnrin wọn.

14 Ọlọ́run mi, rántí mi+ nítorí èyí, má sì gbàgbé ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ tí mo ti fi hàn sí ilé Ọlọ́run mi àti iṣẹ́ ìsìn* rẹ̀.+

15 Ní àkókò yẹn, mo rí àwọn èèyàn ní Júdà tí wọ́n ń fún wáìnì ní Sábáàtì,+ tí wọ́n ń kó òkìtì ọkà wá, tí wọ́n sì ń dì wọ́n lé kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, wọ́n ń kó wáìnì, èso àjàrà àti ọ̀pọ̀tọ́ pẹ̀lú oríṣiríṣi ẹrù wá sí Jerúsálẹ́mù ní ọjọ́ Sábáàtì.+ Torí náà, mo kìlọ̀ fún wọn pé kí wọ́n má ta nǹkan kan lọ́jọ́ náà.* 16 Àwọn ará Tírè tó ń gbé ní ìlú náà ń kó ẹja àti oríṣiríṣi ọjà wá, wọ́n sì ń tà wọ́n fún àwọn èèyàn Júdà àti ní Jerúsálẹ́mù ní ọjọ́ Sábáàtì.+ 17 Torí náà, mo bá àwọn èèyàn pàtàkì ní Júdà wí, mo sì sọ fún wọn pé: “Nǹkan burúkú wo lẹ̀ ń ṣe yìí, tí ẹ̀ ń tẹ òfin Sábáàtì lójú? 18 Ṣé kì í ṣe ohun tí àwọn baba ńlá yín ṣe nìyí tí Ọlọ́run wa fi mú gbogbo àjálù yìí bá àwá àti ìlú yìí? Báyìí, ńṣe lẹ̀ ń dá kún ìbínú tó ń jó fòfò lórí Ísírẹ́lì bí ẹ ò ṣe pa Sábáàtì mọ́.”+

19 Mo pàṣẹ pé kí wọ́n ti àwọn ẹnubodè Jerúsálẹ́mù pa kí ilẹ̀ tó ṣú, ìyẹn kí Sábáàtì tó bẹ̀rẹ̀. Mo tún sọ pé wọn ò gbọ́dọ̀ ṣí wọn títí di ẹ̀yìn Sábáàtì, mo fi lára àwọn ìránṣẹ́ mi sí àwọn ẹnubodè náà kí wọ́n má bàa kó ẹrù kankan wọlé ní ọjọ́ Sábáàtì. 20 Torí náà, ẹ̀yìn òde Jerúsálẹ́mù ni àwọn oníṣòwò àti àwọn tó ń ta oríṣiríṣi ọjà sùn mọ́jú, wọ́n sùn síbẹ̀ lẹ́ẹ̀kan tàbí lẹ́ẹ̀mejì. 21 Lẹ́yìn náà, mo kìlọ̀ fún wọn, mo sì sọ fún wọn pé: “Kí ló dé tí ẹ fi ń sùn níwájú ògiri? Tí ẹ bá tún ṣe bẹ́ẹ̀, màá lé yín kúrò níbẹ̀ tipátipá.” Láti ìgbà yẹn lọ, wọn ò wá lọ́jọ́ Sábáàtì mọ́.

22 Mo wá sọ fún àwọn ọmọ Léfì pé kí wọ́n máa sọ ara wọn di mímọ́, kí wọ́n sì wá máa ṣọ́ àwọn ẹnubodè láti mú kí ọjọ́ Sábáàtì wà ní mímọ́.+ Ọlọ́run mi, jọ̀wọ́ rántí ṣojú rere sí mi nítorí èyí pẹ̀lú, kí o sì ṣàánú mi nínú ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ tí ó pọ̀ gidigidi.+

23 Ní àkókò yẹn, mo rí àwọn Júù tí wọ́n fẹ́ àwọn obìnrin tó jẹ́ ará Áṣídódì,+ ọmọ Ámónì àti ọmọ Móábù.*+ 24 Ìdajì lára àwọn ọmọ wọn ń sọ èdè àwọn ará Áṣídódì, ìdajì tó kù sì ń sọ àwọn èdè míì, kò sí ìkankan nínú wọn tó lè sọ èdè àwọn Júù. 25 Torí náà, mo bá wọn wí, mo sì gégùn-ún fún wọn, mo lu àwọn ọkùnrin kan lára wọn,+ mo fa irun wọn tu, mo sì mú kí wọ́n fi Ọlọ́run búra pé: “Ẹ ò gbọ́dọ̀ fi àwọn ọmọbìnrin yín fún àwọn ọmọkùnrin wọn, ẹ ò sì gbọ́dọ̀ fẹ́ àwọn ọmọbìnrin wọn fún àwọn ọmọkùnrin yín tàbí fún ara yín.+ 26 Ṣé kì í ṣe tìtorí èyí ni Sólómọ́nì ọba Ísírẹ́lì fi dẹ́ṣẹ̀? Kò sí ọba tó dà bíi rẹ̀ láàárín ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè;+ Ọlọ́run rẹ̀ nífẹ̀ẹ́ rẹ̀+ débi pé ó fi í jọba lórí gbogbo Ísírẹ́lì. Síbẹ̀ àwọn àjèjì obìnrin tó fẹ́ mú òun pàápàá dẹ́ṣẹ̀.+ 27 Ṣé ó ṣeé gbọ́ sétí pé ẹ dá ẹ̀ṣẹ̀ ńlá yìí, tí ẹ hùwà àìṣòótọ́ sí Ọlọ́run wa bí ẹ ṣe lọ ń fẹ́ àwọn àjèjì obìnrin?”+

28 Ọ̀kan lára àwọn ọmọkùnrin Jóyádà+ ọmọ Élíáṣíbù  + àlùfáà àgbà ti di àna Sáńbálátì+ tó jẹ́ ará Hórónì. Torí náà, mo lé e kúrò lọ́dọ̀ mi.

29 Ọlọ́run mi, jọ̀wọ́ rántí wọn, nítorí wọ́n ti kó àbààwọ́n bá iṣẹ́ àlùfáà àti májẹ̀mú iṣẹ́ àlùfáà+ àti ti àwọn ọmọ Léfì.+

30 Mo wẹ̀ wọ́n mọ́ kúrò nínú gbogbo ohun àìmọ́ tó jẹ́ ti àwọn àjèjì, mo sì yan iṣẹ́ fún àwọn àlùfáà àti àwọn ọmọ Léfì, kálukú sẹ́nu iṣẹ́ ìsìn rẹ̀,+ 31 mo ṣètò bí wọ́n á ṣe máa kó igi wá+ ní àkókò tí a dá, mo sì tún ṣètò bí wọ́n á ṣe máa kó àkọ́so èso wá.

Ọlọ́run mi, jọ̀wọ́ rántí mi sí rere.*+

Ó túmọ̀ sí “Jáà Ń Tuni Nínú.”

Wo Àfikún B15.

Ìyẹn, Atasásítà.

Tàbí “Súsà.”

Tàbí “ààfin; ibi ààbò.”

Tàbí “agbègbè abẹ́ àṣẹ.”

Tàbí “ìkìlọ̀ tí o fún.”

Wo Àfikún B15.

Tàbí “olorì rẹ̀.”

Tàbí “Òdìkejì odò Yúfírétì.”

Tàbí “igbó ọba.”

Tàbí “Tẹ́ńpìlì.”

Ní Héb., “ìránṣẹ́.”

Ní Héb., “wọ́n fún ọwọ́ ara wọn lókun.”

Ní Héb., “ìránṣẹ́.”

Ní Héb., “kò tẹ ẹ̀yìn ọrùn wọn ba láti ṣe.”

Ní Héb., “tí wọ́n jẹ́ ti ìtẹ́.”

Tàbí “Òdìkejì odò Yúfírétì.”

Tàbí “àwọn tó ń ṣe lọ́fíńdà.”

Tàbí “òkúta palaba-palaba.”

Tàbí “apá kan tí wọ́n wọ̀n.”

Nǹkan bíi mítà 445 (1,460 ẹsẹ̀ bàtà). Wo Àfikún B14.

Ṣélà túmọ̀ sí “Ipa Odò.”

Tàbí kó jẹ́, “agbègbè tó wà nítòsí.”

Tàbí “Ààfin.”

Tàbí “Nétínímù.” Ní Héb., “àwọn tí a fi fúnni.”

Tàbí “Nétínímù.” Ní Héb., “àwọn tí a fi fúnni.”

Tàbí “inú rẹ̀ ru.”

Tàbí “Àwọn arẹrù.”

Ní Héb., “ní ìgbà mẹ́wàá.”

Ní Héb., “ọrun.”

Ní Héb., “ọrun.”

Tàbí “ọṣẹ́.”

Ní Héb., “ọkà.”

Tàbí “owó òde.”

Ní Héb., “Bí ara àwọn arákùnrin wa ṣe rí ni tiwa náà rí.”

Tàbí “èlé gọbọi.”

Tàbí “ìdá kan nínú ọgọ́rùn-ún,” ìyẹn, lóṣooṣù.

Ní Héb., “gbọn àyà mi dà nù.”

Tàbí “Bẹ́ẹ̀ ni kí ó rí!”

Ṣékélì kan jẹ́ gíráàmù 11.4. Wo Àfikún B14.

Tàbí “adìyẹ.”

Tàbí “ni mò ń fún wọn lówó pé kí wọ́n pa fún mi.”

Tàbí “fún ire.”

Wo Àfikún B15.

Ní Héb., “wọ́n ṣubú lulẹ̀ níṣojú ara wọn.”

Tàbí “agbègbè abẹ́ àṣẹ.”

Tàbí “Nétínímù.” Ní Héb., “Àwọn tí a fi fúnni.”

Tàbí “Nétínímù.” Ní Héb., “àwọn tí a fi fúnni.”

Tàbí “wọ́n yọ wọ́n ní ipò àlùfáà torí wọ́n kà wọ́n sí aláìmọ́.”

Tàbí “Tíṣátà,” orúkọ oyè tí àwọn ará Páṣíà fún gómìnà ìpínlẹ̀.

Tàbí “Tíṣátà,” orúkọ oyè tí àwọn ará Páṣíà fún gómìnà ìpínlẹ̀.

Wọ́n gbà pé ó jẹ́ iye kan náà pẹ̀lú owó dáríkì wúrà ilẹ̀ Páṣíà tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ gíráàmù 8.4. Kì í ṣe dírákímà inú Ìwé Mímọ́ Lédè Gíríìkì. Wo Àfikún B14.

Mínà kan nínú Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù jẹ́ gíráàmù 570. Wo Àfikún B14.

Tàbí “Nétínímù.” Ní Héb., “àwọn tí a fi fúnni.”

Ní Héb., “gbogbo Ísírẹ́lì.”

Tàbí “akọ̀wé òfin.”

Tàbí “ìjọ.”

Tàbí “akọ̀wé òfin.”

Tàbí “Bẹ́ẹ̀ ni kí ó rí.”

Tàbí “Tíṣátà,” orúkọ oyè tí àwọn ará Páṣíà fún gómìnà ìpínlẹ̀.

Tàbí “akọ̀wé òfin.”

Ní Héb., “ohun tó lọ́ràá.”

Tàbí “agbára.”

Tàbí “akọ̀wé òfin.”

Tàbí “ìjọ.”

Ní Héb., “aṣọ àpò ìdọ̀họ.”

Ní Héb., “ìdá mẹ́rin ọjọ́.”

Tàbí “láti ayérayé dé ayérayé.”

Ní Héb., “èso.”

Tàbí “àwọsánmà tó rí bí òpó.”

Tàbí “iná tó rí bí òpó.”

Tàbí “àwọn òfin tó ṣeé gbára lé.”

Ní Héb., “tí o gbé ọwọ́ rẹ sókè.”

Ní Héb., “mú kí ọrùn wọn le.”

Ní Héb., “wọ́n mú kí ọrùn wọn le.”

Tàbí “Ọlọ́run ìṣe ìdáríjì.”

Tàbí “olóore ọ̀fẹ́.”

Tàbí “inú rere onífẹ̀ẹ́ rẹ.”

Tàbí “ère dídà.”

Tàbí “àwọsánmà tó rí bí òpó.”

Tàbí “iná tó rí bí òpó.”

Tàbí “ilẹ̀ dáradára.”

Ní Héb., “wọ́n ju Òfin rẹ sí ẹ̀yìn wọn.”

Tàbí “tẹ̀ wọ́n mọ́lẹ̀.”

Tàbí “olóore ọ̀fẹ́.”

Tàbí “ìkìlọ̀.”

Tàbí “ilẹ̀ dáradára.”

Ní Héb., “ara wa.”

Tàbí “Tíṣátà,” orúkọ oyè tí àwọn ará Páṣíà fún gómìnà ìpínlẹ̀.

Tàbí “Nétínímù.” Ní Héb., “àwọn tí a fi fúnni.”

Tàbí kó jẹ́, “àwọn tó dàgbà tó láti lóye.”

Ṣékélì kan jẹ́ gíráàmù 11.4. Wo Àfikún B14.

Tàbí “tẹ́ńpìlì.”

Ìyẹn, búrẹ́dì àfihàn.

Tàbí “àwọn gbọ̀ngàn ìjẹun.”

Tàbí “àwọn gbọ̀ngàn ìjẹun.”

Tàbí “àwọn gbọ̀ngàn ìjẹun.”

Tàbí “agbègbè abẹ́ àṣẹ.”

Tàbí “Nétínímù.” Ní Héb., “àwọn tí a fi fúnni.”

Tàbí “tẹ́ńpìlì.”

Tàbí “lórí ogún rẹ̀.”

Tàbí “Nétínímù.” Ní Héb., “àwọn tí a fi fúnni.”

Tàbí “Nétínímù.” Ní Héb., “àwọn tí a fi fúnni.”

Ní Héb., “wà ní ọwọ́ ọba.”

Tàbí “ìlú tó yí i ká.”

Tàbí “ìlú tó yí i ká.”

Tàbí “ìlú tó yí i ká.”

Tàbí “ìlú tó yí i ká.”

Tàbí “tẹ̀ dó sí.”

Tàbí “ìlú tó yí i ká.”

Tàbí kó jẹ́, “nígbà iṣẹ́ ìsìn.”

Ó ṣe kedere pé àkọsílẹ̀ Hébérù fo orúkọ kan níbí yìí.

Tàbí “akọ̀wé òfin.”

Tàbí “aro.”

Tàbí “àwọn akọrin tó kọ́ṣẹ́ orin.”

Ìyẹn, agbègbè tó yí Jọ́dánì ká.

Tàbí “akọ̀wé òfin.”

Tàbí “iwájú.”

Ní Héb., “àwọn olórí.”

Tàbí “onírúurú èèyàn.”

Tàbí “àwọn gbọ̀ngàn ìjẹun.”

Tàbí “tẹ́ńpìlì.”

Tàbí “gbọ̀ngàn ìjẹun.”

Tàbí “gbọ̀ngàn ìjẹun.”

Tàbí “àwọn gbọ̀ngàn ìjẹun.”

Tàbí “akọ̀wé òfin.”

Tàbí “àbójútó.”

Tàbí kó jẹ́, “lọ́jọ́ náà, mo kìlọ̀ fún wọn pé wọn ò gbọ́dọ̀ ta nǹkan kan.”

Tàbí “tí wọ́n gbé . . . sílé.”

Tàbí “fún ire.”

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́