ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • nwt Hébérù 1:1-13:25
  • Hébérù

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Hébérù
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
Hébérù

SÍ ÀWỌN HÉBÉRÙ

1 Nígbà àtijọ́, Ọlọ́run bá àwọn baba ńlá wa sọ̀rọ̀ nípasẹ̀ àwọn wòlíì lọ́pọ̀ ìgbà àti lọ́pọ̀ ọ̀nà.+ 2 Ní báyìí, ní òpin àwọn ọjọ́ yìí, ó ti bá wa sọ̀rọ̀ nípasẹ̀ Ọmọ+ tó yàn ṣe ajogún ohun gbogbo,+ nípasẹ̀ ẹni tó dá àwọn ètò àwọn nǹkan.*+ 3 Ó ń gbé ògo Ọlọ́run yọ,+ òun ni àwòrán irú ẹni tó jẹ́ gẹ́lẹ́,+ ó sì ń fi ọ̀rọ̀ rẹ̀ tó lágbára gbé ohun gbogbo ró. Lẹ́yìn tó ti wẹ àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa mọ́,+ ó jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún Ọba Ọlọ́lá ní ibi gíga.+ 4 Torí náà, ó ti wá sàn ju àwọn áńgẹ́lì lọ,+ débi pé ó ti jogún orúkọ tó lọ́lá ju tiwọn lọ.+

5 Bí àpẹẹrẹ, èwo nínú àwọn áńgẹ́lì ni Ọlọ́run sọ fún rí pé: “Ìwọ ni ọmọ mi; òní ni mo di bàbá rẹ”?+ Tó sì tún sọ fún pé: “Màá di bàbá rẹ̀, á sì di ọmọ mi”?+ 6 Àmọ́ nígbà tó tún mú Àkọ́bí rẹ̀+ wá sí ilẹ̀ ayé tí à ń gbé, ó sọ pé: “Kí gbogbo áńgẹ́lì Ọlọ́run tẹrí ba* fún un.”

7 Bákan náà, ó sọ nípa àwọn áńgẹ́lì pé: “Ó dá àwọn áńgẹ́lì rẹ̀ ní ẹ̀mí, ó sì dá àwọn òjíṣẹ́ rẹ̀*+ ní ọwọ́ iná.”+ 8 Àmọ́, ó sọ nípa Ọmọ pé: “Ọlọ́run ni ìtẹ́ rẹ+ títí láé àti láéláé, ọ̀pá àṣẹ Ìjọba rẹ sì jẹ́ ọ̀pá àṣẹ ìdúróṣinṣin.* 9 O nífẹ̀ẹ́ òdodo, o sì kórìíra ìwà tí kò bófin mu. Ìdí nìyẹn tí Ọlọ́run, àní Ọlọ́run rẹ, fi fòróró ayọ̀ yàn ọ́+ ju àwọn ojúgbà rẹ.”+ 10 Àti pé: “Ní ìbẹ̀rẹ̀, Olúwa, o fi ìpìlẹ̀ ayé sọlẹ̀, ọ̀run sì jẹ́ iṣẹ́ ọwọ́ rẹ. 11 Wọ́n á ṣègbé, àmọ́ ìwọ á máa wà nìṣó; gbogbo wọn á sì gbó bí aṣọ, 12 o máa ká wọn jọ bí aṣọ àwọ̀lékè, a sì máa pààrọ̀ wọn bí aṣọ. Àmọ́ ìwọ ò yí pa dà, àwọn ọdún rẹ ò sì ní dópin láé.”+

13 Àmọ́ èwo nínú àwọn áńgẹ́lì ló sọ nípa rẹ̀ rí pé: “Jókòó sí ọwọ́ ọ̀tún mi, títí màá fi fi àwọn ọ̀tá rẹ ṣe àpótí ìtìsẹ̀ rẹ”?+ 14 Ṣebí ẹ̀mí tó ń ṣe iṣẹ́ ìsìn mímọ́*+ ni gbogbo wọn, tí a rán jáde láti ṣe ìránṣẹ́ fún àwọn tó máa rí ìgbàlà?

2 Ìdí nìyẹn tó fi yẹ ká túbọ̀ máa fiyè sí àwọn ohun tí a gbọ́,+ ká má bàa sú lọ láé.+ 2 Torí tí ọ̀rọ̀ tí a gbẹnu àwọn áńgẹ́lì sọ+ bá dájú, tí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ àti ìwà àìgbọràn bá sì gba ìyà tó tọ́,+ 3 báwo la ṣe máa bọ́ tí a ò bá ka irú ìgbàlà tó tóbi bẹ́ẹ̀ sí?  + Torí Olúwa wa bẹ̀rẹ̀ sí í sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀,+ àwọn tó gbọ́ ọ lẹ́nu rẹ̀ sì fìdí rẹ̀ múlẹ̀ fún wa, 4 nígbà tí Ọlọ́run náà jẹ́rìí sí i pẹ̀lú àwọn iṣẹ́ àmì àti àwọn iṣẹ́ ìyanu* àti oríṣiríṣi iṣẹ́ agbára,+ tó sì pín ẹ̀mí mímọ́ bó ṣe fẹ́.+

5 Nítorí kò fi ayé tó ń bọ̀ tí à ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ sí ìkáwọ́ àwọn áńgẹ́lì.+ 6 Àmọ́ ibì kan wà tí ẹlẹ́rìí kan ti sọ pé: “Kí ni èèyàn jẹ́ tí o fi ń fi í sọ́kàn tàbí ọmọ aráyé tí o fi ń tọ́jú rẹ̀?+ 7 O mú kí ó rẹlẹ̀ díẹ̀ ju àwọn áńgẹ́lì; o fi ògo àti ọlá dé e ládé, o sì yàn án ṣe olórí àwọn iṣẹ́ ọwọ́ rẹ. 8 O fi ohun gbogbo sábẹ́ ẹsẹ̀ rẹ̀.”+ Bí Ọlọ́run ṣe fi ohun gbogbo sábẹ́ rẹ̀,+ kò sí ohun tí kò fi sábẹ́ rẹ̀.+ Àmọ́, ní báyìí, a ò tíì rí ohun gbogbo lábẹ́ rẹ̀.+ 9 Àmọ́ a rí Jésù, ẹni tí a mú kó rẹlẹ̀ díẹ̀ ju àwọn áńgẹ́lì lọ,+ a ti fi ògo àti ọlá dé e ládé báyìí torí ó jìyà títí ó fi kú,+ kó lè tọ́ ikú wò fún gbogbo èèyàn nípasẹ̀ inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Ọlọ́run.+

10 Torí ó yẹ kí ẹni tí ohun gbogbo torí rẹ̀ wà, tí ohun gbogbo sì tipasẹ̀ rẹ̀ wà, bí o ti ń mú ọ̀pọ̀ ọmọ wá sínú ògo,+ sọ Olórí Aṣojú ìgbàlà+ wọn di pípé nípasẹ̀ ìjìyà.+ 11 Torí ọ̀dọ̀ ẹnì kan ni ẹni tó ń sọni di mímọ́ àti àwọn tí à ń sọ di mímọ́+ ti wá,+ torí èyí ni ojú ò ṣe tì í láti pè wọ́n ní arákùnrin,+ 12 bó ṣe sọ pé: “Màá sọ orúkọ rẹ fún àwọn arákùnrin mi; màá sì fi orin yìn ọ́ láàárín ìjọ.”+ 13 Ó tún sọ pé: “Màá gbẹ́kẹ̀ lé e.”+ Àti pé: “Wò ó! Èmi àti àwọn ọmọ kéékèèké tí Jèhófà* fún mi.”+

14 Nítorí náà, torí pé “àwọn ọmọ kéékèèké” ní ẹ̀jẹ̀ àti ẹran ara, òun náà wá ní ẹ̀jẹ̀ àti ẹran ara,+ kó lè tipasẹ̀ ikú rẹ̀ pa ẹni tó lè fa ikú run,+ ìyẹn Èṣù,+ 15 kó sì lè dá àwọn tí ìbẹ̀rù ikú ti mú lẹ́rú ní gbogbo ìgbésí ayé wọn sílẹ̀.*+ 16 Torí kì í ṣe àwọn áńgẹ́lì ló ń ràn lọ́wọ́, àmọ́ ọmọ* Ábúráhámù ló ń ràn lọ́wọ́.+ 17 Bákan náà, ó ní láti dà bí “àwọn arákùnrin” rẹ̀ ní gbogbo ọ̀nà,+ kó lè di àlùfáà àgbà tó jẹ́ aláàánú àti olóòótọ́ nínú àwọn ohun tó jẹ mọ́ ti Ọlọ́run, kó lè rú ẹbọ ìpẹ̀tù*+ fún ẹ̀ṣẹ̀ àwọn èèyàn.+ 18 Torí pé òun fúnra rẹ̀ ti jìyà nígbà tí a dán an wò,+ ó lè ran àwọn tí à ń dán wò lọ́wọ́.+

3 Torí náà, ẹ̀yin ará tí ẹ jẹ́ mímọ́, ẹ̀yin tí ẹ ní ìpè* ti ọ̀run,+ ẹ ronú nípa àpọ́sítélì àti àlùfáà àgbà tí a gbà,* ìyẹn Jésù.+ 2 Ó jẹ́ olóòótọ́ sí Ẹni tó yàn án,+ bí Mósè náà ṣe jẹ́ ní gbogbo ilé Ẹni yẹn.+ 3 Torí a kà á* yẹ pé kó ní ògo+ tó ju ti Mósè lọ, nítorí ẹni tó kọ́lé máa ń ní ọlá ju ilé lọ. 4 Ó dájú pé, gbogbo ilé ló ní ẹni tó kọ́ ọ, àmọ́ Ọlọ́run ló kọ́ ohun gbogbo. 5 Mósè jẹ́ ìránṣẹ́ olóòótọ́ ní gbogbo ilé Ẹni yẹn, gẹ́gẹ́ bí ẹ̀rí* àwọn ohun tí a máa sọ lẹ́yìn náà, 6 àmọ́ Kristi jẹ́ olóòótọ́ ọmọ+ lórí ilé Ọlọ́run. Àwa ni ilé Rẹ̀,+ tí a bá rí i dájú pé a ò jẹ́ kí ohunkóhun dí wa lọ́wọ́ láti máa sọ̀rọ̀ ní fàlàlà, tí a sì di ìrètí tí a fi ń yangàn mú ṣinṣin títí dé òpin.

7 Torí náà, bí ẹ̀mí mímọ́ ṣe sọ pé,+ “Lónìí, tí ẹ bá fetí sí ohùn rẹ̀, 8 ẹ má ṣe mú kí ọkàn yín le bó ṣe rí nígbà tí ẹ fa ìbínú tó le gan-an, bíi ti ọjọ́ tí ẹ fa àdánwò ní aginjù,+ 9 níbi tí àwọn baba ńlá yín ti dán mi wò, tí wọ́n sì dẹ mí wò, láìka àwọn iṣẹ́ mi tí wọ́n rí fún ogójì (40) ọdún sí.+ 10 Ìdí nìyẹn tí ọ̀rọ̀ ìran yìí fi kó mi nírìíra, tí mo sì sọ pé: ‘Àwọn èèyàn tó máa ń ṣìnà nínú ọkàn ni wọ́n, wọn ò sì tíì mọ àwọn ọ̀nà mi.’ 11 Torí náà, mo búra nínú ìbínú mi pé, ‘Wọn ò ní wọnú ìsinmi mi.’”+

12 Ẹ̀yin ará, ẹ ṣọ́ra, kí ẹnì kankan nínú yín má lọ ní ọkàn burúkú tí kò ní ìgbàgbọ́, tí á mú kó fi Ọlọ́run alààyè sílẹ̀;+ 13 àmọ́ ẹ máa fún ara yín níṣìírí lójoojúmọ́, tí a bá ṣì ń pè é ní “Òní,”+ kí agbára ìtannijẹ ẹ̀ṣẹ̀ má bàa sọ ìkankan nínú yín di ọlọ́kàn líle. 14 Torí àfi tí a bá ní irú ìdánilójú tí a ní níbẹ̀rẹ̀ títí dé òpin, la máa fi lè ní ìpín pẹ̀lú Kristi.*+ 15 Bí a ṣe sọ ọ́ pé, “Lónìí, tí ẹ bá fetí sí ohùn rẹ̀, ẹ má ṣe mú kí ọkàn yín le bó ṣe rí nígbà tí ẹ fa ìbínú tó le gan-an.”+

16 Torí, àwọn wo ló gbọ́, síbẹ̀ tí wọ́n mú un bínú gidigidi? Ní tòótọ́, ṣebí gbogbo àwọn tí Mósè kó jáde ní Íjíbítì ni?+ 17 Bákan náà, àwọn wo ni ọ̀rọ̀ wọn kó Ọlọ́run nírìíra fún ogójì (40) ọdún?+ Ṣebí àwọn tó dẹ́ṣẹ̀, tí òkú wọn sùn nínú aginjù ni?+ 18 Àwọn wo ló sì búra fún pé wọn ò ní wọnú ìsinmi òun? Ṣebí àwọn tó ṣàìgbọràn ni? 19 Torí náà, a rí i pé àìnígbàgbọ́ ò jẹ́ kí wọ́n lè wọnú rẹ̀.+

4 Torí náà, nígbà tó jẹ́ pé ìlérí tó ṣe pé a máa wọnú ìsinmi òun ṣì wà, ẹ jẹ́ ká ṣọ́ra,* kó má bàa di pé ẹnì kan nínú yín ò kúnjú ìwọ̀n rẹ̀.+ 2 Torí wọ́n ti kéde ìhìn rere fún àwa náà,+ bíi tiwọn; àmọ́ ọ̀rọ̀ tí wọ́n gbọ́ ò ṣe wọ́n láǹfààní, torí ìgbàgbọ́ wọn ò bá ti àwọn tó fetí sílẹ̀ mu. 3 Torí àwa tí a ní ìgbàgbọ́ wọnú ìsinmi náà, bó ṣe sọ pé: “Torí náà, mo búra nínú ìbínú mi pé, ‘Wọn ò ní wọnú ìsinmi mi,’”+ bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn iṣẹ́ rẹ̀ ti parí látìgbà ìpìlẹ̀ ayé.+ 4 Torí ibì kan wà tó ti sọ nípa ọjọ́ keje pé: “Ọlọ́run sì sinmi ní ọjọ́ keje lẹ́yìn gbogbo iṣẹ́ rẹ̀,”+ 5 ó tún sọ níbí yìí pé: “Wọn ò ní wọnú ìsinmi mi.”+

6 Torí náà, nígbà tó jẹ́ pé àwọn kan ò tíì wọnú rẹ̀, tí àwọn tó kọ́kọ́ gbọ́ ìhìn rere ò sì wọnú rẹ̀ torí àìgbọràn,+ 7 bó ṣe sọ pé, “Òní” nínú sáàmù ti Dáfídì lẹ́yìn ọ̀pọ̀ àkókò, ó tún sàmì sí ọjọ́ kan pàtó; bẹ́ẹ̀ náà la sọ ṣáájú pé, “Lónìí, tí ẹ bá fetí sí ohùn rẹ̀, ẹ má ṣe mú kí ọkàn yín le.”+ 8 Torí ká ní Jóṣúà+ ti mú wọn dé ibi ìsinmi ni, Ọlọ́run ò tún ní sọ̀rọ̀ ọjọ́ míì lẹ́yìn náà. 9 Torí náà, ìsinmi sábáàtì kan ṣì wà fún àwọn èèyàn Ọlọ́run.+ 10 Torí ẹni tó wọnú ìsinmi Ọlọ́run ti sinmi pẹ̀lú lẹ́yìn àwọn iṣẹ́ rẹ̀, bí Ọlọ́run ṣe sinmi lẹ́yìn iṣẹ́ tirẹ̀.+

11 Torí náà, ẹ jẹ́ ká sa gbogbo ipá wa láti wọnú ìsinmi yẹn, kí ẹnì kankan má bàa kó sínú irú ìwà àìgbọràn kan náà.+ 12 Torí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run wà láàyè, ó sì ní agbára,+ ó mú ju idà olójú méjì èyíkéyìí lọ,+ ó sì ń gúnni, àní débi pé ó ń pín ọkàn* àti ẹ̀mí* níyà, ó ń pín àwọn oríkèé àti mùdùnmúdùn sọ́tọ̀ọ̀tọ̀, ó sì lè mọ ìrònú àti ohun tí ọkàn ń gbèrò. 13 Kò sí ìṣẹ̀dá kankan tó fara pa mọ́ ní ojú rẹ̀,+ àmọ́ ohun gbogbo wà ní ìhòòhò, ó sì wà ní gbangba lójú ẹni tí a gbọ́dọ̀ jíhìn fún.+

14 Torí náà, nígbà tó jẹ́ pé àlùfáà àgbà tó tóbi la ní, ẹni tó ti la ọ̀run kọjá, Jésù Ọmọ Ọlọ́run,+ ẹ jẹ́ ká máa kéde rẹ̀ ní gbangba.+ 15 Torí àlùfáà àgbà tí a ní kì í ṣe ẹni tí kò lè bá wa kẹ́dùn fún àwọn àìlera wa,+ àmọ́ ó jẹ́ ẹni tí a ti dán wò ní gbogbo ọ̀nà bíi tiwa, àmọ́ tí kò ní ẹ̀ṣẹ̀.+ 16 Torí náà, ẹ jẹ́ ká sún mọ́ ìtẹ́ inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí, ká sọ̀rọ̀ ní fàlàlà,+ ká lè rí àánú gbà, ká sì rí inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí tó máa ràn wá lọ́wọ́ ní àkókò tó tọ́.

5 Torí gbogbo àlùfáà àgbà tí a mú láàárín àwọn èèyàn ni a yàn nítorí wọn láti bójú tó àwọn ohun tó jẹ mọ́ Ọlọ́run,+ kó lè fi àwọn ọrẹ àti ẹbọ rúbọ nítorí ẹ̀ṣẹ̀.+ 2 Ó ṣeé ṣe fún un láti ṣàánú àwọn aláìmọ̀kan* àti àwọn tó ń ṣàṣìṣe,* torí òun náà ní àìlera tiẹ̀,* 3 ìdí nìyẹn tí òun náà fi gbọ́dọ̀ rú ẹbọ nítorí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tiẹ̀, bó ṣe ń ṣe nítorí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn èèyàn gẹ́lẹ́.+

4 Èèyàn kì í fún ara rẹ̀ ní irú ọlá yìí, àfi tí Ọlọ́run bá pè é ló máa rí i gbà, bíi ti Áárónì.+ 5 Bákan náà, Kristi kọ́ ló ṣe ara rẹ̀ lógo  + nígbà tó di àlùfáà àgbà, àmọ́ Ẹni tó sọ fún un pé: “Ìwọ ni ọmọ mi; òní ni mo di bàbá rẹ”+ ló ṣe é lógo. 6 Ó tún sọ ní ibòmíì pé, “Ìwọ jẹ́ àlùfáà títí láé ní ọ̀nà ti Melikisédékì.”+

7 Nígbà tí Kristi wà ní ayé,* ó rawọ́ ẹ̀bẹ̀, ó sì fi ẹkún tó rinlẹ̀ àti omijé tọrọ+ lọ́wọ́ Ẹni tó lè gbà á lọ́wọ́ ikú, a sì gbọ́ ọ, a ṣojúure sí i torí pé ó ní ìbẹ̀rù Ọlọ́run. 8 Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ọmọ ni, ó kọ́ ìgbọràn látinú ìyà tó jẹ.+ 9 Lẹ́yìn tí a sì sọ ọ́ di pípé,+ ipasẹ̀ rẹ̀ ni gbogbo àwọn tó ń ṣègbọràn sí i fi máa ní ìgbàlà àìnípẹ̀kun,+ 10 torí Ọlọ́run ti fi ṣe àlùfáà àgbà ní ọ̀nà ti Melikisédékì.+

11 A ní ohun tó pọ̀ láti sọ nípa rẹ̀, ó sì ṣòroó ṣàlàyé, torí pé ẹ kì í fọkàn sí ohun tí ẹ̀ ń gbọ́ mọ́.* 12 Torí, bó tiẹ̀ jẹ́ pé ó yẹ kí ẹ ti di olùkọ́ báyìí,* ẹ ṣì tún nílò kí ẹnì kan máa kọ́ yín láti ìbẹ̀rẹ̀ nípa àwọn ohun àkọ́bẹ̀rẹ̀+ tó wà nínú àwọn ọ̀rọ̀ ìkéde mímọ́ ti Ọlọ́run, ẹ sì ti pa dà di ẹni tó nílò wàrà, kì í ṣe oúnjẹ líle. 13 Torí gbogbo ẹni tí kò yéé mu wàrà kò mọ ọ̀rọ̀ òdodo, torí pé ọmọdé ni.+ 14 Àmọ́ àwọn tó dàgbà ni oúnjẹ líle wà fún, àwọn tó ti kọ́ agbára ìfòyemọ̀* wọn nípa bí wọ́n ṣe ń lò ó láti fi ìyàtọ̀ sáàárín ohun tó tọ́ àti ohun tí kò tọ́.

6 Torí náà, ní báyìí tí a ti kọjá àwọn ẹ̀kọ́ àkọ́bẹ̀rẹ̀+ nípa Kristi, ẹ jẹ́ ká tẹ̀ síwájú, ká dàgbà nípa tẹ̀mí,+ ká má ṣe tún máa fi ìpìlẹ̀ lélẹ̀ mọ́, ìyẹn ìrònúpìwàdà kúrò nínú àwọn òkú iṣẹ́ àti ìgbàgbọ́ nínú Ọlọ́run, 2 ẹ̀kọ́ nípa ìrìbọmi àti gbígbé ọwọ́ léni,+ àjíǹde àwọn òkú+ àti ìdájọ́ àìnípẹ̀kun. 3 A sì máa ṣe èyí, tó bá jẹ́ pé ohun tí Ọlọ́run fẹ́ ká ṣe nìyẹn lóòótọ́.

4 Torí ní ti àwọn tí a ti là lóye rí,+ tí wọ́n ti tọ́ ẹ̀bùn ọ̀fẹ́ ti ọ̀run wò, tí wọ́n sì ti ní ìpín nínú ẹ̀mí mímọ́, 5 tí wọ́n ti tọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tó jẹ́ ọ̀rọ̀ àtàtà wò àti agbára ètò àwọn nǹkan tó ń bọ̀,* 6 àmọ́ tí wọ́n yẹsẹ̀,+ kò ṣeé ṣe láti tún mú wọn sọ jí kí wọ́n lè ronú pìwà dà, torí ṣe ni wọ́n tún kan Ọmọ Ọlọ́run mọ́gi* fún ara wọn, wọ́n sì dójú tì í ní gbangba.+ 7 Ilẹ̀ máa ń gba ìbùkún Ọlọ́run tó bá fa omi òjò tó ń rọ̀ sí i déédéé mu, ó sì máa mú ewéko jáde, èyí tó máa wúlò fún àwọn tí wọ́n ń ro ó fún. 8 Àmọ́ tó bá jẹ́ ẹ̀gún àti òṣùṣú ló ń mú jáde, a máa pa á tì, ó sì ṣeé ṣe ká gégùn-ún fún un, a sì máa dáná sun ún nígbẹ̀yìn-gbẹ́yín.

9 Àmọ́ ní tiyín, ẹ̀yin ará mi ọ̀wọ́n, bí a tiẹ̀ ń sọ̀rọ̀ lọ́nà yìí, àwọn ohun tó dáa jù ló dá wa lójú, àwọn ohun tó jẹ mọ́ ìgbàlà. 10 Torí Ọlọ́run kì í ṣe aláìṣòdodo tó fi máa gbàgbé iṣẹ́ yín àti ìfẹ́ tí ẹ fi hàn fún orúkọ rẹ̀ + bí ẹ ṣe ń ṣe ìránṣẹ́ fún àwọn ẹni mímọ́, tí ẹ sì ń bá a lọ láti ṣe ìránṣẹ́. 11 Àmọ́, ó wù wá kí ẹnì kọ̀ọ̀kan yín máa ṣiṣẹ́ kára bẹ́ẹ̀, kí ìrètí náà lè dá yín lójú+ ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ títí dé òpin,+ 12 kí ẹ má bàa máa lọ́ra,+ àmọ́ kí ẹ lè máa tẹ̀ lé àpẹẹrẹ àwọn tí ìgbàgbọ́ àti sùúrù mú kí wọ́n jogún àwọn ìlérí náà.

13 Torí nígbà tí Ọlọ́run ṣe ìlérí fún Ábúráhámù, ó fi ara rẹ̀ búra, nígbà tó jẹ́ pé kò sí ẹlòmíì tó tóbi jù ú lọ tó lè fi búra,+ 14 ó sọ pé: “Ó dájú pé màá bù kún ọ, ó sì dájú pé màá mú kí o di púpọ̀.”+ 15 Torí náà, lẹ́yìn tí Ábúráhámù ní sùúrù, ó rí ìlérí yìí gbà. 16 Torí àwọn èèyàn máa ń fi ẹni tó tóbi jù wọ́n lọ búra, ìbúra wọn sì máa ń fòpin sí gbogbo awuyewuye, torí ó ń fìdí ọ̀rọ̀ wọn múlẹ̀ lábẹ́ òfin.+ 17 Lọ́nà kan náà, nígbà tí Ọlọ́run pinnu láti jẹ́ kó túbọ̀ ṣe kedere sí àwọn ajogún ìlérí+ náà pé ohun tí òun ní lọ́kàn* kò lè yí pa dà, ó búra* kó lè fìdí rẹ̀ múlẹ̀, 18 kó lè jẹ́ pé nípasẹ̀ àwọn nǹkan méjì tí kò lè yí pa dà, tí Ọlọ́run ò ti lè parọ́,+ àwa tí a ti sá sí ibi ààbò máa lè rí ìṣírí tó lágbára gbà láti di ìrètí tó wà níwájú wa mú ṣinṣin. 19 A ní ìrètí yìí+ bí ìdákọ̀ró fún ọkàn,* ó dájú, ó fìdí múlẹ̀, ó sì wọlé sẹ́yìn aṣọ ìdábùú,+ 20 níbi tí aṣíwájú kan ti wọ̀ nítorí wa, ìyẹn Jésù,+ ẹni tó ti di àlùfáà àgbà ní ọ̀nà ti Melikisédékì títí láé.+

7 Nítorí Melikisédékì yìí, ọba Sálẹ́mù, àlùfáà Ọlọ́run Gíga Jù Lọ, pàdé Ábúráhámù nígbà tó ń pa dà bọ̀ látibi tó ti pa àwọn ọba, ó sì súre fún un,+ 2 Ábúráhámù wá fún un ní ìdá mẹ́wàá gbogbo nǹkan.* Lákọ̀ọ́kọ́ ná, ìtúmọ̀ orúkọ rẹ̀ ni “Ọba Òdodo,” bákan náà, ọba Sálẹ́mù, ìyẹn “Ọba Àlàáfíà.” 3 Bó ṣe jẹ́ pé kò ní bàbá, kò ní ìyá, kò ní ìran, kò ní ìbẹ̀rẹ̀ ọjọ́, kò sì ní òpin ìwàláàyè, àmọ́ tí a ṣe é bí Ọmọ Ọlọ́run, ó jẹ́ àlùfáà títí láé.*+

4 Ẹ wo bí ọkùnrin yìí ṣe tóbi tó, ẹni tí Ábúráhámù, olórí ìdílé,* fún ní ìdá mẹ́wàá àwọn ẹrù ogun tó dáa jù.+ 5 Lóòótọ́, bí Òfin ṣe sọ, a pàṣẹ fún àwọn ọmọ Léfì+ tí wọ́n gba iṣẹ́ àlùfáà wọn pé kí wọ́n máa gba ìdá mẹ́wàá lọ́wọ́ àwọn èèyàn,+ ìyẹn lọ́wọ́ àwọn arákùnrin wọn, bí àwọn yìí tiẹ̀ jẹ́ àtọmọdọ́mọ* Ábúráhámù. 6 Àmọ́ ọkùnrin yìí tí kò wá láti ìran wọn gba ìdá mẹ́wàá lọ́wọ́ Ábúráhámù, ó sì súre fún ẹni tí a ṣèlérí fún.+ 7 Torí náà, ó ṣe kedere pé ẹni tí ó tóbi súre fún ẹni tí ó kéré. 8 Àti pé nínú ọ̀rọ̀ àkọ́kọ́, àwọn èèyàn tó ń kú ló ń gba ìdá mẹ́wàá, àmọ́ nínú ọ̀rọ̀ kejì, ẹnì kan tí a jẹ́rìí nípa rẹ̀ pé ó wà láàyè ni.+ 9 A sì lè sọ pé Léfì tó ń gba ìdá mẹ́wàá pàápàá ti san ìdá mẹ́wàá nípasẹ̀ Ábúráhámù, 10 torí àtọmọdọ́mọ tí a kò tíì bí ló ṣì jẹ́ sí* baba ńlá rẹ̀ nígbà tí Melikisédékì pàdé rẹ̀.+

11 Tó bá jẹ́ pé iṣẹ́ àlùfáà+ àwọn ọmọ Léfì lè mú ìjẹ́pípé wá ni (torí ó wà lára Òfin tí a fún àwọn èèyàn), ṣé a tún máa nílò kí àlùfáà míì dìde, ẹni tí a sọ pé ó wà ní ọ̀nà ti Melikisédékì,+ tí kì í ṣe ní ọ̀nà ti Áárónì? 12 Torí nígbà tí a ti yí ètò ṣíṣe àlùfáà pa dà, ó di dandan ká yí Òfin náà pa dà.+ 13 Torí ẹ̀yà míì ni ọkùnrin tí a sọ àwọn nǹkan yìí nípa rẹ̀ ti wá, ẹnì kankan látinú ẹ̀yà náà ò sì ṣiṣẹ́ nídìí pẹpẹ rí.+ 14 Torí ó ṣe kedere pé ọ̀dọ̀ Júdà ni Olúwa wa ti ṣẹ̀ wá,+ síbẹ̀, Mósè ò sọ pé àlùfáà kankan máa wá látinú ẹ̀yà yẹn.

15 Èyí wá túbọ̀ ṣe kedere nígbà tí àlùfáà+ míì tó dà bíi Melikisédékì+ dìde, 16 ẹni tó jẹ́ pé kì í ṣe ohun tí òfin sọ nípa ibi tí èèyàn ti ṣẹ̀ wá ló mú kó rí bẹ́ẹ̀, àmọ́ ó jẹ́ nípasẹ̀ agbára ìwàláàyè tí kò ṣeé pa run.+ 17 Torí a jẹ́rìí nípa rẹ̀ pé: “Ìwọ jẹ́ àlùfáà títí láé ní ọ̀nà ti Melikisédékì.”+

18 Torí náà, a pa àṣẹ ti tẹ́lẹ̀ tì torí pé kò lágbára, kò sì gbéṣẹ́ mọ́.+ 19 Torí Òfin ò sọ ohunkóhun di pípé,+ àmọ́ ìrètí tó dáa jù+ tó wọlé wá ṣe bẹ́ẹ̀, èyí tí à ń tipasẹ̀ rẹ̀ sún mọ́ Ọlọ́run.+ 20 Bákan náà, nígbà tó jẹ́ pé a ò ṣe èyí láìsí ìbúra 21 (torí ní tòótọ́, àwọn èèyàn wà tí wọ́n ti di àlùfáà láìsí ìbúra, àmọ́ ti ẹni yìí rí bẹ́ẹ̀ nípasẹ̀ ìbúra tí a ṣe nípa rẹ̀ látọ̀dọ̀ Ẹni tó sọ pé: “Jèhófà* ti búra, kò sì ní pèrò dà,* ó ní, ‘Ìwọ jẹ́ àlùfáà títí láé’”),+ 22 Jésù wá tipa bẹ́ẹ̀ di ẹni tó fìdí májẹ̀mú tó dáa jù múlẹ̀.*+ 23 Bákan náà, ó di dandan kí ọ̀pọ̀ di àlùfáà tẹ̀ léra+ torí pé ikú ò jẹ́ kí wọ́n lè máa bá iṣẹ́ náà lọ, 24 àmọ́ torí pé òun wà láàyè títí láé,+ kò sí pé ẹnì kan ń rọ́pò rẹ̀ lẹ́nu iṣẹ́ àlùfáà. 25 Èyí jẹ́ kó lè gba àwọn tó ń tipasẹ̀ rẹ̀ wá sọ́dọ̀ Ọlọ́run là pátápátá, torí ó wà láàyè nígbà gbogbo láti bá wọn bẹ̀bẹ̀.+

26 Torí irú àlùfáà àgbà yìí ló yẹ wá, ẹni tó jẹ́ adúróṣinṣin, aláìṣẹ̀, aláìlẹ́gbin,+ ẹni tí a yà sọ́tọ̀ láàárín àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀, tí a sì gbé ga ju ọ̀run lọ.+ 27 Kò nílò kó máa rúbọ lójoojúmọ́,+ bíi ti àwọn àlùfáà àgbà yẹn, fún àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tiẹ̀ lákọ̀ọ́kọ́, lẹ́yìn náà fún ẹ̀ṣẹ̀ àwọn èèyàn,+ torí ó ti ṣe èyí nígbà tó fi ara rẹ̀ rúbọ lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo láìtún ní ṣe é mọ́ láé.+ 28 Torí àwọn èèyàn tó ní àìlera ni Òfin ń yàn ṣe àlùfáà àgbà,+ àmọ́ Ọmọ ni ọ̀rọ̀ ìbúra+ tí a ṣe lẹ́yìn Òfin yàn, ẹni tí a ti sọ di pípé+ títí láé.

8 Kókó ọ̀rọ̀ tí à ń sọ nìyí: A ní irú àlùfáà àgbà yìí,+ ó sì ti jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún ìtẹ́ Ọba Ọlọ́lá ní ọ̀run,+ 2 òjíṣẹ́* ibi mímọ́+ àti àgọ́ tòótọ́, tí Jèhófà* gbé kalẹ̀, kì í ṣe èèyàn. 3 Torí gbogbo àlùfáà àgbà la yàn láti máa fi àwọn ọrẹ àti ẹbọ rúbọ; torí náà, ó pọn dandan fún ẹni yìí náà pé kó ní ohun kan láti fi rúbọ.+ 4 Tó bá jẹ́ pé ayé ló wà, kò ní jẹ́ àlùfáà,+ torí àwọn èèyàn tó ń fi ọrẹ rúbọ bí Òfin ṣe sọ ti wà. 5 Àwọn èèyàn yìí ń ṣe iṣẹ́ ìsìn mímọ́ bí àpẹẹrẹ àti òjìji+ àwọn nǹkan ti ọ̀run;+ bí a ṣe pàṣẹ fún Mósè láti ọ̀run, nígbà tó fẹ́ kọ́ àgọ́ náà pé: Torí Ó sọ pé: “Rí i pé o ṣe gbogbo nǹkan bí ohun tí mo fi hàn ọ́ lórí òkè.”+ 6 Àmọ́ ní báyìí, Jésù ti gba iṣẹ́ òjíṣẹ́* tó lọ́lá jùyẹn lọ torí òun tún ni alárinà+ májẹ̀mú tó dáa jù,+ tó sì bá a mu rẹ́gí, èyí tí a ti fìdí rẹ̀ múlẹ̀ lọ́nà òfin lórí àwọn ìlérí tó dáa jù.+

7 Ká sọ pé májẹ̀mú àkọ́kọ́ yẹn ò ní àléébù ni, a ò ní nílò ìkejì.+ 8 Torí ó ń rí àléébù lára àwọn èèyàn nígbà tó sọ pé: “‘Wò ó! Ọjọ́ ń bọ̀,’ ni Jèhófà* wí, ‘tí màá bá ilé Ísírẹ́lì àti ilé Júdà dá májẹ̀mú tuntun. 9 Kò ní dà bíi májẹ̀mú tí mo bá àwọn baba ńlá wọn dá ní ọjọ́ tí mo dì wọ́n lọ́wọ́ mú láti mú wọn kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì,+ torí pé wọn ò pa májẹ̀mú mi mọ́, ìdí nìyẹn tí mi ò fi bójú tó wọn mọ́,’ ni Jèhófà* wí.

10 “‘Nítorí májẹ̀mú tí màá bá ilé Ísírẹ́lì dá lẹ́yìn ìgbà yẹn nìyí,’ ni Jèhófà* wí. ‘Màá fi àwọn òfin mi sínú èrò wọn, inú ọkàn wọn sì ni màá kọ ọ́ sí.+ Màá di Ọlọ́run wọn, wọ́n á sì di èèyàn mi.+

11 “‘Kálukú wọn kò tún ní máa kọ́ ọmọ ìbílẹ̀ rẹ̀ àti arákùnrin rẹ̀ mọ́ pé: “Ẹ mọ Jèhófà!”* Nítorí gbogbo wọn á mọ̀ mí, látorí ẹni tó kéré jù lọ dórí ẹni tó tóbi jù lọ láàárín wọn. 12 Torí màá ṣàánú wọn lórí ọ̀rọ̀ ìwà àìṣòdodo wọn, mi ò sì ní rántí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wọn mọ́.’”+

13 Bó ṣe pè é ní “májẹ̀mú tuntun,” ó ti sọ èyí tó wà tẹ́lẹ̀ di èyí tí kò wúlò mọ́.+ Ní báyìí, èyí tí kò wúlò mọ́, tó sì ti ń gbó lọ máa tó pa rẹ́ pátápátá.+

9 Ní tirẹ̀, májẹ̀mú ti tẹ́lẹ̀ ní àwọn ohun tí òfin béèrè, fún iṣẹ́ ìsìn mímọ́ àti ibi mímọ́+ rẹ̀ ní ayé. 2 Torí wọ́n kọ́ apá àkọ́kọ́ nínú àgọ́, níbi tí ọ̀pá fìtílà,+ tábìlì àti àwọn búrẹ́dì tí wọ́n ń gbé síwájú*+ wà; a sì ń pè é ní Ibi Mímọ́.+ 3 Àmọ́ lẹ́yìn aṣọ ìdábùú kejì,+ apá kan wà tí à ń pè ní Ibi Mímọ́ Jù Lọ.+ 4 Àwo tùràrí oníwúrà+ àti àpótí májẹ̀mú  + tí wọ́n fi wúrà bò látòkè délẹ̀+ wà níbẹ̀, inú rẹ̀ ni ìṣà wúrà tí wọ́n kó mánà+ sí wà pẹ̀lú ọ̀pá Áárónì tó yọ òdòdó+ àti àwọn wàláà+ májẹ̀mú; 5 àwọn kérúbù ológo tí wọ́n ṣíji bo ìbòrí ìpẹ̀tù*+ sì wà lórí rẹ̀. Àmọ́ àkókò kọ́ nìyí láti máa sọ kúlẹ̀kúlẹ̀ àwọn nǹkan yìí.

6 Lẹ́yìn tí wọ́n kọ́ àwọn nǹkan yìí lọ́nà yìí, àwọn àlùfáà máa ń wọ apá àkọ́kọ́ nínú àgọ́ náà déédéé kí wọ́n lè ṣe àwọn iṣẹ́ ìsìn mímọ́;+ 7 àmọ́ àlùfáà àgbà nìkan ló máa ń wọ apá kejì lẹ́ẹ̀kan lọ́dún,+ kì í wọ ibẹ̀ láìsí ẹ̀jẹ̀,+ èyí tó fi máa ń rúbọ fún ara rẹ̀+ àti fún ẹ̀ṣẹ̀ táwọn èèyàn+ dá láìmọ̀ọ́mọ̀. 8 Ẹ̀mí mímọ́ tipasẹ̀ èyí fi hàn kedere pé a ò tíì fi ọ̀nà tó wọnú ibi mímọ́ hàn nígbà tí àgọ́ àkọ́kọ́ ṣì wà.+ 9 Àgọ́ yìí jẹ́ àpèjúwe fún àkókò yìí,+ a sì ń fi àwọn ọrẹ àti ẹbọ rúbọ ní ìbámu pẹ̀lú ètò yìí.+ Àmọ́ àwọn yìí ò lè mú kí ẹni tó ń ṣe iṣẹ́ ìsìn mímọ́ ní ẹ̀rí ọkàn tó mọ́ pátápátá.+ 10 Kìkì ohun tí wọ́n dá lé lórí ni oúnjẹ, ohun mímu àti oríṣiríṣi ìwẹ̀* tí òfin sọ.+ Wọ́n jẹ́ àwọn ohun tí òfin béèrè ní ti ara,+ a sì sọ ọ́ di dandan títí di àkókò tí a yàn láti mú àwọn nǹkan tọ́.

11 Àmọ́, nígbà tí Kristi dé bí àlùfáà àgbà àwọn ohun rere tó ti ṣẹlẹ̀, ó gba inú àgọ́ tó tóbi jù, tó sì jẹ́ pípé jù, tí wọn ò fi ọwọ́ ṣe, ìyẹn tí kì í ṣe ti ẹ̀dá yìí. 12 Kì í ṣe ẹ̀jẹ̀ ewúrẹ́ àti ti àwọn akọ ọmọ màlúù ló gbé wọnú ibi mímọ́, àmọ́ ẹ̀jẹ̀ òun fúnra rẹ̀ ni,+ lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo láìtún ní ṣe é mọ́ láé, ó sì gba ìtúsílẹ̀* àìnípẹ̀kun fún wa.+ 13 Torí tí ẹ̀jẹ̀ àwọn ewúrẹ́ àti ti àwọn akọ màlúù+ àti eérú ọmọ màlúù* tí wọ́n fi wọ́n àwọn tó ti di aláìmọ́ bá sọ wọ́n di mímọ́ kó lè wẹ ẹran ara mọ́,+ 14 ǹjẹ́ ẹ̀jẹ̀ Kristi,+ ẹni tó tipasẹ̀ ẹ̀mí àìnípẹ̀kun fi ara rẹ̀ rúbọ sí Ọlọ́run láìní àbààwọ́n kò ní ṣe jù bẹ́ẹ̀ lọ láti wẹ ẹ̀rí ọkàn wa mọ́ kúrò nínú àwọn òkú iṣẹ́,+ ká lè máa ṣe iṣẹ́ ìsìn mímọ́ fún Ọlọ́run alààyè?+

15 Ìdí nìyẹn tó fi jẹ́ alárinà májẹ̀mú tuntun,+ kí àwọn tí a ti pè lè gba ìlérí ogún àìnípẹ̀kun, torí ẹnì kan ti kú fún wọn, kí wọ́n lè rí ìtúsílẹ̀ nípasẹ̀ ìràpadà+ kúrò lọ́wọ́ àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tó wà lábẹ́ májẹ̀mú ti tẹ́lẹ̀.+ 16 Torí tí a bá dá májẹ̀mú, ẹ̀rí gbọ́dọ̀ wà pé èèyàn tó dá májẹ̀mú náà ti kú, 17 ìdí ni pé ikú máa ń fìdí májẹ̀mú múlẹ̀, torí pé kò tíì lè bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ tí èèyàn tó dá májẹ̀mú náà bá ṣì wà láàyè. 18 Tó bá rí bẹ́ẹ̀, májẹ̀mú ti tẹ́lẹ̀ náà kò lè ṣiṣẹ́* láìsí ẹ̀jẹ̀. 19 Torí lẹ́yìn tí Mósè sọ gbogbo àṣẹ inú Òfin náà fún gbogbo èèyàn, ó mú ẹ̀jẹ̀ àwọn akọ ọmọ màlúù àti ti àwọn ewúrẹ́, pẹ̀lú omi, òwú aláwọ̀ rírẹ̀dòdò àti ewéko hísópù, ó sì fi wọ́n ìwé* náà àti gbogbo àwọn èèyàn náà, 20 ó sọ pé: “Èyí ni ẹ̀jẹ̀ májẹ̀mú tí Ọlọ́run pa láṣẹ pé kí ẹ pa mọ́.”+ 21 Bákan náà, ó fi ẹ̀jẹ̀ náà wọ́n àgọ́ àti gbogbo ohun tí wọ́n ń lò fún iṣẹ́ ìsìn mímọ́.*+ 22 Àní bí Òfin ṣe sọ, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé gbogbo nǹkan ni wọ́n ń fi ẹ̀jẹ̀ wẹ̀ mọ́,+ ìdáríjì kankan ò sì lè wáyé àfi tí a bá tú ẹ̀jẹ̀ jáde.+

23 Torí náà, ó pọn dandan pé ká wẹ àwọn ohun tó ṣàpẹẹrẹ+ àwọn ohun ti ọ̀run mọ́ láwọn ọ̀nà yìí,+ àmọ́ àwọn ẹbọ tó dáa ju èyí lọ fíìfíì ló yẹ àwọn ohun ti ọ̀run. 24 Torí Kristi ò wọnú ibi mímọ́ tí wọ́n fi ọwọ́ ṣe,+ tó jẹ́ àpẹẹrẹ ohun gidi,+ àmọ́ ọ̀run gangan ló wọ̀ lọ,+ tó fi jẹ́ pé ó ń fara hàn báyìí níwájú* Ọlọ́run nítorí wa.+ 25 Kò ṣe èyí láti máa fi ara rẹ̀ rúbọ léraléra bí ìgbà tí àlùfáà àgbà máa ń wọ ibi mímọ́ lọ́dọọdún+ pẹ̀lú ẹ̀jẹ̀ tí kì í ṣe tiẹ̀. 26 Àìjẹ́ bẹ́ẹ̀, ì bá máa jìyà léraléra látìgbà ìpìlẹ̀ ayé. Àmọ́ ní báyìí, ó ti fi ara rẹ̀ hàn kedere ní ìparí àwọn ètò àwọn nǹkan,* lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo láìtún ní ṣe é mọ́ láé, ó fi ara rẹ̀ rúbọ kó lè mú ẹ̀ṣẹ̀ kúrò.+ 27 Bó ṣe jẹ́ pé ẹ̀ẹ̀kan ṣoṣo ni èèyàn máa ń kú, tí kò sì ní kú mọ́ láé, àmọ́ lẹ́yìn èyí, ó máa gba ìdájọ́, 28 bákan náà ló ṣe jẹ́ pé a fi Kristi rúbọ lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo láìtún ní ṣe é mọ́ láé, kó lè ru ẹ̀ṣẹ̀ ọ̀pọ̀lọpọ̀;+ tó bá sì fara hàn lẹ́ẹ̀kejì, kò ní jẹ́ torí ẹ̀ṣẹ̀,* àwọn tó ń fi taratara wá a fún ìgbàlà wọn sì máa rí i.+

10 Nígbà tó jẹ́ pé Òfin ní òjìji+ àwọn nǹkan rere tó ń bọ̀,+ àmọ́ tí kì í ṣe bí àwọn nǹkan náà ṣe máa rí gan-an, kò lè* sọ àwọn tó ń wá sí tòsí di pípé láé nípasẹ̀ àwọn ẹbọ kan náà tí wọ́n ń rú léraléra láti ọdún dé ọdún.+ 2 Tí kò bá rí bẹ́ẹ̀, ṣé wọn ò ti ní dáwọ́ rírú àwọn ẹbọ náà dúró? Torí tí a bá ti wẹ àwọn tó ń ṣe iṣẹ́ ìsìn mímọ́ mọ́ lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo, wọn ò ní mọ̀ ọ́n lára pé àwọn jẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀ mọ́. 3 Kàkà bẹ́ẹ̀, ṣe ni àwọn ẹbọ yìí ń ránni létí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ láti ọdún dé ọdún,+ 4 torí ẹ̀jẹ̀ àwọn akọ màlúù àti ti àwọn ewúrẹ́ kò lè mú àwọn ẹ̀ṣẹ̀ kúrò.

5 Torí náà, nígbà tó wá sí ayé, ó sọ pé: “‘Ẹbọ àti ọrẹ kọ́ ni ohun tí o fẹ́, àmọ́ ìwọ pèsè ara kan fún mi. 6 O ò fọwọ́ sí àwọn odindi ẹbọ sísun àti ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀.’+ 7 Lẹ́yìn náà, mo sọ pé: ‘Wò ó! Mo ti dé (a ti kọ ọ́ nípa mi sínú àkájọ ìwé*) láti ṣe ìfẹ́ rẹ, Ọlọ́run.’”+ 8 Lẹ́yìn tó kọ́kọ́ sọ pé: “O ò fẹ́ àwọn ẹbọ, ọrẹ, odindi ẹbọ sísun àti ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, o ò sì fọwọ́ sí i”—àwọn ẹbọ tí wọ́n ń rú, bí Òfin ṣe sọ— 9 ó wá sọ pé: “Wò ó! Mo ti dé láti ṣe ìfẹ́ rẹ.”+ Ó fi òpin sí èyí àkọ́kọ́ kó lè fìdí ìkejì múlẹ̀. 10 Nípasẹ̀ “ìfẹ́” yìí,+ a ti fi ara Jésù Kristi tó fi rúbọ lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo láìtún ní ṣe é mọ́ láé sọ wá di mímọ́.+

11 Bákan náà, gbogbo àwọn àlùfáà máa ń lọ sẹ́nu iṣẹ́ wọn lójoojúmọ́ kí wọ́n lè ṣe iṣẹ́ ìsìn mímọ́,*+ kí wọ́n sì lè rú àwọn ẹbọ kan náà léraléra,+ èyí tí kò lè mú ẹ̀ṣẹ̀ kúrò pátápátá.+ 12 Àmọ́ ẹbọ kan ṣoṣo ni ọkùnrin yìí rú fún ẹ̀ṣẹ̀ láìtún ní ṣe é mọ́ láé, ó sì jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún Ọlọ́run,+ 13 látìgbà yẹn, ó ń dúró de ìgbà tí a máa fi àwọn ọ̀tá rẹ̀ ṣe àpótí ìtìsẹ̀ rẹ̀.+ 14 Torí ẹbọ kan ṣoṣo tó rú ló fi sọ àwọn tí à ń sọ di mímọ́ di pípé+ láìtún ní ṣe é mọ́ láé. 15 Bákan náà, ẹ̀mí mímọ́ náà ń jẹ́rìí fún wa, torí lẹ́yìn tó sọ pé: 16 “‘Májẹ̀mú tí màá bá wọn dá lẹ́yìn ìgbà yẹn nìyí,’ ni Jèhófà* wí. ‘Màá fi àwọn òfin mi sínú ọkàn wọn, inú èrò wọn ni màá sì kọ ọ́ sí.’”+ 17 Ó wá sọ pé: “Mi ò sì ní rántí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wọn mọ́ àti àwọn ìwà wọn tí kò bófin mu.”+ 18 Torí náà, tí a bá ti dárí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ yìí jini, kò tún sí ẹbọ nítorí ẹ̀ṣẹ̀ mọ́.

19 Torí náà, ẹ̀yin ará, nígbà tó jẹ́ pé a ní ìgboyà* láti wá sí ọ̀nà tó wọnú ibi mímọ́+ nípasẹ̀ ẹ̀jẹ̀ Jésù, 20 èyí tó ṣí sílẹ̀* fún wa bí ọ̀nà tuntun, tó sì jẹ́ ọ̀nà ìyè tó la aṣọ ìdábùú kọjá,+ ìyẹn ẹran ara rẹ̀, 21 nígbà tó sì jẹ́ pé a ní àlùfáà ńlá lórí ilé Ọlọ́run,+ 22 ẹ jẹ́ ká fi ọkàn tòótọ́ àti ìgbàgbọ́ tó kún rẹ́rẹ́ wá, nígbà tí a ti wẹ ọkàn wa mọ́ kúrò nínú ẹ̀rí ọkàn burúkú,+ tí a sì ti fi omi tó mọ́ wẹ ara wa.+ 23 Ẹ jẹ́ ká tẹra mọ́ ìkéde ìrètí wa ní gbangba* láìṣiyèméjì,+ torí pé olóòótọ́ ni ẹni tó ṣèlérí. 24 Ẹ sì jẹ́ ká gba ti ara wa rò* ká lè máa fún ara wa níṣìírí* láti ní ìfẹ́ àti láti ṣe àwọn iṣẹ́ rere,+ 25 ká má ṣe máa kọ ìpàdé wa sílẹ̀,+ bí àṣà àwọn kan, àmọ́ ká máa gba ara wa níyànjú,+ ní pàtàkì jù lọ bí ẹ ṣe ń rí i pé ọjọ́ náà ń sún mọ́lé.+

26 Torí tí a bá mọ̀ọ́mọ̀ sọ ẹ̀ṣẹ̀ dàṣà lẹ́yìn tí a ti gba ìmọ̀ tó péye nípa òtítọ́,+ kò tún sí ẹbọ kankan fún ẹ̀ṣẹ̀ mọ́,+ 27 àfi ká máa fi ìbẹ̀rù retí ìdájọ́ àti ìbínú tó le, tó sì máa jó àwọn tó ń ṣàtakò run.+ 28 A kì í ṣàánú ẹnikẹ́ni tí kò bá ka Òfin Mósè sí, ó máa kú tí ẹni méjì tàbí mẹ́ta bá ti jẹ́rìí sí i.+ 29 Báwo lẹ ṣe wá rò pé ó yẹ kí ìyà tó máa jẹ ẹni tó tẹ Ọmọ Ọlọ́run mọ́lẹ̀ pọ̀ tó, tó ti ka ẹ̀jẹ̀ májẹ̀mú+ tí a fi sọ ọ́ di mímọ́ sí nǹkan yẹpẹrẹ, tó sì fi ìwà àfojúdi mú ẹ̀mí inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí bínú?+ 30 Torí a mọ Ẹni tó sọ pé: “Tèmi ni ẹ̀san; màá gbẹ̀san.” Àti pé: “Jèhófà* máa dá ẹjọ́ àwọn èèyàn rẹ̀.”+ 31 Ohun tó ń bani lẹ́rù ló jẹ́ láti kó sí ọwọ́ Ọlọ́run alààyè.

32 Àmọ́, ẹ máa rántí àwọn ọjọ́ àtijọ́, tí ẹ fara da ìjàkadì ńlá pẹ̀lú ìyà, lẹ́yìn tí a là yín lóye.+ 33 Nígbà míì, wọ́n máa ń tú yín síta gbangba* fún ẹ̀gàn àti ìpọ́njú, nígbà míì sì rèé, ẹ máa ń ṣe alábàápín pẹ̀lú* àwọn tí irú nǹkan bẹ́ẹ̀ ṣẹlẹ̀ sí. 34 Torí ẹ bá àwọn tó wà ní ẹ̀wọ̀n kẹ́dùn, ẹ sì fi ayọ̀ gba bí wọ́n ṣe kó ẹrù yín,+ torí ẹ mọ̀ pé ẹ̀yin fúnra yín ní ohun ìní tó dáa jù, tó sì wà pẹ́ títí.+

35 Torí náà, ẹ má sọ ìgboyà yín* nù, èyí tí a máa torí rẹ̀ fún yín ní èrè tó kún rẹ́rẹ́.+ 36 Nítorí ẹ nílò ìfaradà,+ pé lẹ́yìn tí ẹ ti ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run, kí ẹ lè rí ohun tí ó ṣèlérí náà gbà. 37 Torí ní “ìgbà díẹ̀ sí i”+ àti pé “ẹni tó ń bọ̀ máa dé, kò sì ní pẹ́.”+ 38 “Àmọ́ ìgbàgbọ́ yóò mú kí olódodo mi wà láàyè”+ àti pé “tó bá fà sẹ́yìn, inú mi* ò ní dùn sí i.”+ 39 Ní báyìí, a kì í ṣe irú àwọn tó ń fà sẹ́yìn sí ìparun,+ àmọ́ irú àwọn tó ní ìgbàgbọ́ kí a lè dá ẹ̀mí* wa sí.

11 Ìgbàgbọ́ ni ìdánilójú* ohun tí à ń retí,+ ẹ̀rí tó dájú* nípa àwọn ohun gidi tí a kò rí. 2 Torí àwọn èèyàn àtijọ́* rí ẹ̀rí nípasẹ̀ rẹ̀.

3 Ìgbàgbọ́ jẹ́ ká mọ̀ pé ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ló mú kí àwọn ètò àwọn nǹkan* wà létòlétò, tó fi jẹ́ pé ohun tí à ń rí jáde wá látinú àwọn ohun tí a kò rí.

4 Ìgbàgbọ́ mú kí Ébẹ́lì rú ẹbọ tó níye lórí ju ti Kéènì+ lọ sí Ọlọ́run, ìgbàgbọ́ náà sì mú kó rí ẹ̀rí pé ó jẹ́ olódodo, torí Ọlọ́run fọwọ́ sí* àwọn ẹ̀bùn rẹ̀,+ bó tiẹ̀ kú, ó ṣì ń sọ̀rọ̀+ nípasẹ̀ ìgbàgbọ́ rẹ̀.

5 Ìgbàgbọ́ mú ká ṣí Énọ́kù+ nípò pa dà kó má bàa rí ikú, a ò sì rí i níbì kankan torí pé Ọlọ́run ti ṣí i nípò pa dà;+ torí ká tó ṣí i nípò pa dà, ó rí ẹ̀rí pé ó ti ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run dáadáa. 6 Bákan náà, láìsí ìgbàgbọ́ kò ṣeé ṣe láti ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run dáadáa, torí ẹnikẹ́ni tó bá ń tọ Ọlọ́run wá gbọ́dọ̀ gbà gbọ́ pé ó wà àti pé òun ló ń san èrè fún àwọn tó ń wá a tọkàntọkàn.+

7 Ìgbàgbọ́ mú kí Nóà  + fi ìbẹ̀rù Ọlọ́run hàn, lẹ́yìn tó gba ìkìlọ̀ láti ọ̀run nípa àwọn ohun tí a kò tíì rí,+ ó kan ọkọ̀ áàkì+ kí agbo ilé rẹ̀ lè rí ìgbàlà; ó dá ayé lẹ́bi nípasẹ̀ ìgbàgbọ́ yìí,+ ó sì di ajogún òdodo irú èyí tí ìgbàgbọ́ ń mú wá.

8 Ìgbàgbọ́ mú kí Ábúráhámù+ ṣègbọràn nígbà tí a pè é, ó lọ sí ibì kan tó máa gbà, tó sì máa jogún; ó jáde lọ, bí kò tiẹ̀ mọ ibi tó ń lọ.+ 9 Ìgbàgbọ́ mú kó máa gbé bí àjèjì ní ilẹ̀ ìlérí, bíi pé ó jẹ́ ilẹ̀ àjèjì,+ ó ń gbé inú àgọ́ + pẹ̀lú Ísákì àti Jékọ́bù, àwọn tí wọ́n jọ jẹ́ ajogún ìlérí kan náà.+ 10 Torí ó ń retí ìlú tó ní ìpìlẹ̀ tòótọ́, tí Ọlọ́run ṣètò,* tó sì kọ́.+

11 Ìgbàgbọ́ mú kí Sérà náà gba agbára láti lóyún ọmọ,* kódà nígbà tí ọjọ́ orí rẹ̀ ti kọjá ti ẹni tó lè bímọ,+ torí ó ka Ẹni tó ṣe ìlérí náà sí olóòótọ́.* 12 Torí èyí, nípasẹ̀ ọkùnrin kan tó ti ń kú lọ,+ a bí àwọn ọmọ + tó pọ̀ bí ìràwọ̀ ojú ọ̀run, tí wọn ò sì ṣeé kà bí iyanrìn etí òkun.+

13 Gbogbo àwọn yìí ní ìgbàgbọ́ títí wọ́n fi kú, bí wọn ò tiẹ̀ rí àwọn ohun tí ó ṣèlérí náà gbà;  + àmọ́ wọ́n rí i láti òkèèrè,+ wọ́n tẹ́wọ́ gbà á, wọ́n sì kéde ní gbangba pé àwọn jẹ́ àjèjì àti olùgbé fún ìgbà díẹ̀* ní ilẹ̀ náà. 14 Torí àwọn tó ń sọ̀rọ̀ lọ́nà yẹn jẹ́ kó ṣe kedere pé tọkàntọkàn ni àwọn ń wá ibi tó jẹ́ tiwọn. 15 Síbẹ̀, tó bá jẹ́ pé wọ́n ṣì ń rántí ibi tí wọ́n ti kúrò ni,+ àyè ì bá ṣí sílẹ̀ fún wọn láti pa dà. 16 Àmọ́ ní báyìí, wọ́n ń sapá láti dé ibi tó dáa jù, ìyẹn èyí tó jẹ́ ti ọ̀run. Torí náà, Ọlọ́run ò tijú, pé kí wọ́n máa pe òun ní Ọlọ́run wọn,+ torí ó ti ṣètò ìlú kan sílẹ̀ fún wọn.+

17 Nígbà tí a dán Ábúráhámù wò,+ ká kúkú sọ pé ó ti fi Ísákì rúbọ tán torí ìgbàgbọ́—ọkùnrin tó gba àwọn ìlérí náà tayọ̀tayọ̀ fẹ́ fi ọmọkùnrin kan ṣoṣo tó bí rúbọ+— 18 bó tiẹ̀ jẹ́ pé a ti sọ fún un pé: “Látọ̀dọ̀ Ísákì+ ni ọmọ* rẹ yóò ti wá.” 19 Àmọ́, ó ronú pé Ọlọ́run lè gbé e dìde tó bá tiẹ̀ kú, ó sì rí i gbà láti ibẹ̀ lọ́nà àpèjúwe.+

20 Ìgbàgbọ́ mú kí Ísákì náà súre fún Jékọ́bù+ àti Ísọ̀+ nípa àwọn ohun tó ń bọ̀.

21 Ìgbàgbọ́ mú kí Jékọ́bù súre fún àwọn ọmọkùnrin Jósẹ́fù+ níkọ̀ọ̀kan nígbà tó fẹ́ kú,+ ó sì jọ́sìn bó ṣe sinmi lé orí ọ̀pá rẹ̀.+

22 Ìgbàgbọ́ mú kí Jósẹ́fù sọ̀rọ̀ nípa ìgbà tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì máa jáde lọ bí ọjọ́ ikú rẹ̀ ṣe ń sún mọ́lé, ó sì fún wọn ní ìtọ́ni* nípa àwọn egungun rẹ̀.*+

23 Ìgbàgbọ́ mú kí àwọn òbí Mósè gbé e pa mọ́ fún oṣù mẹ́ta lẹ́yìn tí wọ́n bí i,+ torí wọ́n rí i pé ọmọ kékeré náà rẹwà,+ wọn ò sì bẹ̀rù àṣẹ ọba.+ 24 Ìgbàgbọ́ mú kí Mósè kọ̀ kí wọ́n máa pe òun ní ọmọ ọmọbìnrin Fáráò+ nígbà tó dàgbà,+ 25 ó yàn pé kí wọ́n fìyà jẹ òun pẹ̀lú àwọn èèyàn Ọlọ́run dípò kó jẹ ìgbádùn ẹ̀ṣẹ̀ tí kì í tọ́jọ́, 26 torí pé ó ka ẹ̀gàn Kristi sí ọrọ̀ tó tóbi ju àwọn ìṣúra Íjíbítì lọ, torí ó tẹjú mọ́ gbígba èrè náà. 27 Ìgbàgbọ́ mú kó kúrò ní Íjíbítì,+ àmọ́ kò bẹ̀rù ìbínú ọba,+ torí ó dúró ṣinṣin bíi pé ó ń rí Ẹni tí a kò lè rí.+ 28 Ìgbàgbọ́ mú kó ṣe Ìrékọjá, ó sì wọ́n ẹ̀jẹ̀, kí apanirun má bàa pa àwọn àkọ́bí wọn lára.*+

29 Ìgbàgbọ́ mú kí wọ́n la Òkun Pupa kọjá bíi pé ilẹ̀ gbígbẹ ni,+ àmọ́ nígbà tí àwọn ará Íjíbítì dán an wò, omi gbé wọn mì.+

30 Ìgbàgbọ́ mú kí àwọn ògiri Jẹ́ríkò wó lulẹ̀ lẹ́yìn tí àwọn èèyàn náà fi ọjọ́ méje yan yí ibẹ̀ ká.+ 31 Ìgbàgbọ́ Ráhábù aṣẹ́wó kò jẹ́ kó ṣègbé pẹ̀lú àwọn tó ṣàìgbọràn, torí ó gba àwọn amí náà tọwọ́tẹsẹ̀.+

32 Kí ni kí n tún sọ? Torí àkókò ò ní tó tí n bá ní kí n máa sọ̀rọ̀ nípa Gídíónì,+ Bárákì,+ Sámúsìn,+ Jẹ́fútà,+ Dáfídì,+ títí kan Sámúẹ́lì+ àti àwọn wòlíì yòókù. 33 Ìgbàgbọ́ mú kí wọ́n ṣẹ́gun àwọn ìjọba,+ wọ́n mú kí òdodo fìdí múlẹ̀, wọ́n rí àwọn ìlérí gbà,+ wọ́n dí ẹnu àwọn kìnnìún,+ 34 wọ́n dáwọ́ agbára iná dúró,+ wọ́n bọ́ lọ́wọ́ ojú idà,+ a sọ wọ́n di alágbára nígbà tí wọ́n jẹ́ aláìlera,+ wọ́n di akíkanjú lójú ogun,+ wọ́n mú kí àwọn ọmọ ogun ọ̀tá sá lọ.+ 35 Àwọn obìnrin rí àwọn òkú wọn gbà nípa àjíǹde,+ àmọ́ wọ́n dá àwọn ọkùnrin míì lóró torí pé wọn ò gbà kí wọ́n tú àwọn sílẹ̀ nípasẹ̀ ìràpadà, kí ọwọ́ wọn lè tẹ àjíǹde tó dáa jù. 36 Àní, àdánwò tí àwọn míì kojú ni pé wọ́n fi wọ́n ṣẹlẹ́yà, wọ́n sì nà wọ́n lẹ́gba, kódà ó jùyẹn lọ, wọ́n fi ṣẹkẹ́ṣẹkẹ̀ dè wọ́n,+ wọ́n sì fi wọ́n sẹ́wọ̀n.+ 37 Wọ́n sọ wọ́n lókùúta,+ wọ́n dán wọn wò, wọ́n fi ayùn rẹ́ wọn sí méjì,* wọ́n fi idà pa wọ́n,+ wọ́n rìn kiri pẹ̀lú awọ àgùntàn àti awọ ewúrẹ́ lọ́rùn,+ nígbà tí wọ́n ṣaláìní, nínú ìpọ́njú,+ nígbà tí wọ́n hùwà àìdáa sí wọn;+ 38 ayé ò sì yẹ wọ́n. Wọ́n rìn káàkiri nínú àwọn aṣálẹ̀, lórí àwọn òkè, nínú àwọn ihò àpáta àti àwọn ihò inú ilẹ̀.+

39 Síbẹ̀, bí a tiẹ̀ jẹ́rìí tó dáa nípa gbogbo àwọn yìí torí ìgbàgbọ́ wọn, wọn ò rí ohun tó ṣèlérí náà gbà, 40 torí pé Ọlọ́run ti rí ohun tó dáa jù fún wa ṣáájú,+ kí a má bàa sọ wọ́n di pípé láìsí àwa.

12 Nígbà náà, torí pé a ní àwọsánmà àwọn ẹlẹ́rìí tó pọ̀ gan-an yí wa ká, ẹ jẹ́ kí àwa náà ju gbogbo ẹrù tó wúwo nù àti ẹ̀ṣẹ̀ tó máa ń wé mọ́ wa tìrọ̀rùn-tìrọ̀rùn,+ ká sì máa fi ìfaradà sá eré ìje tó wà níwájú wa,+ 2 bí a ṣe ń tẹjú mọ́ Jésù, Olórí Aṣojú àti Aláṣepé ìgbàgbọ́ wa.+ Torí ayọ̀ tó wà níwájú rẹ̀, ó fara da òpó igi oró,* kò ka ìtìjú sí, ó sì ti jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún ìtẹ́ Ọlọ́run.+ 3 Ní tòótọ́, ẹ fara balẹ̀ ronú nípa ẹni tó fara da irú ọ̀rọ̀ kòbákùngbé bẹ́ẹ̀ láti ẹnu àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀,+ tí wọ́n ń ṣàkóbá fún ara wọn, kó má bàa rẹ̀ yín, kí ẹ má sì sọ̀rètí nù.*+

4 Bí ẹ ṣe ń bá ẹ̀ṣẹ̀ yẹn jà, ẹ ò tíì ta kò ó débi pé kí wọ́n ta ẹ̀jẹ̀ yín sílẹ̀ rárá. 5 Ẹ sì ti gbàgbé ọ̀rọ̀ ìyànjú náà pátápátá, tó fi bá yín sọ̀rọ̀ bí ọmọ pé: “Ọmọ mi, má fojú kéré ìbáwí látọ̀dọ̀ Jèhófà,* má sì sọ̀rètí nù nígbà tó bá tọ́ ọ sọ́nà; 6 torí àwọn tí Jèhófà* nífẹ̀ẹ́ ló máa ń bá wí, àní, gbogbo ẹni tó gbà bí ọmọ ló máa ń nà lẹ́gba.”*+

7 Ẹ nílò ìfaradà bí ẹ ṣe ń gba ìbáwí.* Ọlọ́run mú yín bí ọmọ.+ Torí ọmọ wo ni bàbá kì í bá wí?+ 8 Àmọ́ tí gbogbo yín ò bá tíì pín nínú ìbáwí yìí, a jẹ́ pé ọmọ àlè ni yín, ẹ kì í ṣe ọmọ. 9 Bákan náà, àwọn bàbá tó bí wa* máa ń bá wa wí, a sì máa ń bọ̀wọ̀ fún wọn. Ṣé kò wá yẹ kó yá wa lára láti fi ara wa sábẹ́ Baba tó ni ìgbésí ayé wa nípa ti ẹ̀mí, ká lè máa wà láàyè?+ 10 Torí ìgbà díẹ̀ ni wọ́n fi ń bá wa wí, bó ṣe dáa lójú wọn, àmọ́ torí ire wa ni òun ṣe ń ṣe bẹ́ẹ̀, ká lè pín nínú ìjẹ́mímọ́ rẹ̀.+ 11 Lóòótọ́, kò sí ìbáwí tó jẹ́ ohun ayọ̀ báyìí, àmọ́ ó máa ń dunni;* síbẹ̀, tó bá yá, ó máa ń so èso àlàáfíà ti òdodo fún àwọn tí a ti fi dá lẹ́kọ̀ọ́.

12 Torí náà, ẹ fún àwọn ọwọ́ tó rọ jọwọrọ àti àwọn orúnkún tí kò lágbára lókun,+ 13 kí ẹ sì máa ṣe ọ̀nà tó tọ́ fún ẹsẹ̀ yín,+ kí ohun tó rọ má bàa yẹ̀ kúrò ní oríkèé, àmọ́ ká lè wò ó sàn. 14 Ẹ máa lépa àlàáfíà pẹ̀lú gbogbo èèyàn+ àti ìsọdimímọ́,*+ tó jẹ́ pé láìsí i, èèyàn kankan ò lè rí Olúwa. 15 Ẹ kíyè sára gidigidi ká má bàa rí ẹnikẹ́ni tí kò ní gba inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Ọlọ́run, kí gbòǹgbò kankan tó ní májèlé má bàa rú yọ láti dá wàhálà sílẹ̀, kó sì sọ ọ̀pọ̀ di aláìmọ́;+ 16 kí ẹ sì máa kíyè sára, kó má bàa sí ẹnì kankan láàárín yín tó jẹ́ oníṣekúṣe* tàbí ẹnikẹ́ni tí kò mọyì àwọn ohun mímọ́, bí Ísọ̀, tó fi àwọn ẹ̀tọ́ àkọ́bí tó ní tọrẹ nítorí oúnjẹ ẹ̀ẹ̀kan ṣoṣo.+ 17 Torí ẹ mọ̀ pé lẹ́yìn náà, nígbà tó fẹ́ gba ìbùkún náà, a kọ̀ ọ́; torí bó tiẹ̀ sunkún bó ṣe gbìyànjú gan-an láti mú kí èrò yí pa dà,*+ pàbó ló já sí.*

18 Torí kì í ṣe ohun tó ṣeé fọwọ́ bà,+ tí a sì dáná sí,+ lẹ sún mọ́, kì í ṣe ìkùukùu* tó ṣú dùdù àti òkùnkùn biribiri àti ìjì,+ 19 àti ìró kàkàkí+ àti ohùn tó ń sọ̀rọ̀,+ èyí tó jẹ́ pé nígbà tí àwọn èèyàn náà gbọ́ ọ, wọ́n bẹ̀bẹ̀ pé ká má ṣe bá àwọn sọ̀rọ̀ mọ́.+ 20 Torí wọn ò lè mú àṣẹ náà mọ́ra pé: “Tí ẹranko pàápàá bá fara kan òkè náà, ẹ gbọ́dọ̀ sọ ọ́ lókùúta.”+ 21 Bákan náà, ohun tí wọ́n rí bani lẹ́rù débi pé Mósè sọ pé: “Ẹ̀rù ń bà mí, jìnnìjìnnì sì bò mí.”+ 22 Àmọ́ ẹ ti sún mọ́ Òkè Síónì+ àti ìlú Ọlọ́run alààyè, Jerúsálẹ́mù ti ọ̀run+ àti ọ̀kẹ́ àìmọye* àwọn áńgẹ́lì 23 tí wọ́n kóra jọ+ àti ìjọ àwọn àkọ́bí tí a ti kọ orúkọ wọn sílẹ̀ ní ọ̀run àti Ọlọ́run Onídàájọ́ gbogbo ẹ̀dá+ àti ìgbésí ayé àwọn olódodo nípa ti ẹ̀mí,+ àwọn tí a ti sọ di pípé+ 24 àti Jésù alárinà+ májẹ̀mú tuntun  + àti ẹ̀jẹ̀ tí a wọ́n, tó ń sọ̀rọ̀ lọ́nà tó dáa ju ẹ̀jẹ̀ Ébẹ́lì lọ.+

25 Ẹ rí i pé ẹ ò di etí yín sí* ẹni tó ń sọ̀rọ̀.* Torí tí àwọn tó kọ̀ láti fetí sí ẹni tó ń kéde ìkìlọ̀ Ọlọ́run ní ayé kò bá yè bọ́, báwo wá ni àwa ṣe lè yè bọ́ tí a bá yí pa dà kúrò lọ́dọ̀ ẹni tó ń sọ̀rọ̀ láti ọ̀run!+ 26 Nígbà yẹn, ohùn rẹ̀ mi ayé jìgìjìgì,+ àmọ́ ní báyìí, ó ti ṣèlérí pé: “Lẹ́ẹ̀kan sí i, kì í ṣe ayé nìkan ni màá mì jìgìjìgì, màá mi ọ̀run pẹ̀lú.”+ 27 Ọ̀rọ̀ náà “lẹ́ẹ̀kan sí i” tọ́ka sí i pé a máa mú àwọn ohun tí a mì kúrò, àwọn ohun tí a ti ṣe, kí àwọn ohun tí a ò mì lè dúró. 28 Torí náà, bí a ṣe rí i pé a máa tẹ́wọ́ gba Ìjọba kan tí kò ṣeé mì, ẹ jẹ́ ká túbọ̀ máa gba inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí, èyí tí a lè tipasẹ̀ rẹ̀ ṣe iṣẹ́ ìsìn mímọ́ tí Ọlọ́run máa tẹ́wọ́ gbà pẹ̀lú ìbẹ̀rù Ọlọ́run àti ọ̀wọ̀. 29 Torí Ọlọ́run wa jẹ́ iná tó ń jóni run.+

13 Ẹ túbọ̀ máa ní ìfẹ́ ará.+ 2 Ẹ má gbàgbé láti máa ṣe aájò àlejò,*+ torí àwọn kan ti tipa bẹ́ẹ̀ ṣe àwọn áńgẹ́lì lálejò láìmọ̀.+ 3 Ẹ máa rántí àwọn tó wà nínú ẹ̀wọ̀n,*+ bí ẹni pé ẹ jọ wà lẹ́wọ̀n+ àti àwọn tí wọ́n ń fìyà jẹ, torí pé ẹ̀yin fúnra yín náà wà nínú ara.* 4 Kí ìgbéyàwó ní ọlá láàárín gbogbo èèyàn, kí ibùsùn ìgbéyàwó má sì ní ẹ̀gbin,+ torí Ọlọ́run máa dá àwọn oníṣekúṣe* àti àwọn alágbèrè lẹ́jọ́.+ 5 Ẹ yẹra fún ìfẹ́ owó nínú ìgbésí ayé yín,+ bí ẹ ṣe ń jẹ́ kí àwọn nǹkan tó wà báyìí tẹ́ yín lọ́rùn.+ Torí ó ti sọ pé: “Mi ò ní fi ọ́ sílẹ̀ láé, mi ò sì ní pa ọ́ tì láé.”+ 6 Ká lè nígboyà gidigidi, ká sì sọ pé: “Jèhófà* ni olùrànlọ́wọ́ mi; mi ò ní bẹ̀rù. Kí ni èèyàn lè fi mí ṣe?”+

7 Ẹ máa rántí àwọn tó ń mú ipò iwájú láàárín yín,+ tí wọ́n ti sọ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fún yín, bí ẹ sì ṣe ń ṣàyẹ̀wò bí ìwà wọn ṣe rí, ẹ máa tẹ̀ lé àpẹẹrẹ ìgbàgbọ́ wọn.+

8 Ọ̀kan náà ni Jésù Kristi lánàá, lónìí àti títí láé.

9 Ẹ má ṣe jẹ́ kí wọ́n fi oríṣiríṣi ẹ̀kọ́ àtàwọn ẹ̀kọ́ tó ṣàjèjì ṣì yín lọ́nà, torí ó sàn kí inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí fún ọkàn lókun ju oúnjẹ* lọ, èyí tí kì í ṣàǹfààní fún àwọn tó gbà lọ́kàn.+

10 A ní pẹpẹ kan, tí àwọn tó ń ṣe iṣẹ́ ìsìn mímọ́ níbi àgọ́ kò láṣẹ láti jẹ níbẹ̀.+ 11 Torí wọ́n máa ń sun ara àwọn ẹran tí àlùfáà àgbà máa ń mú ẹ̀jẹ̀ wọn wọnú ibi mímọ́ láti fi rú ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ lẹ́yìn ibùdó.+ 12 Torí náà, Jésù náà jìyà lẹ́yìn odi* ìlú+ kó lè fi ẹ̀jẹ̀ ara rẹ̀ sọ àwọn èèyàn di mímọ́.+ 13 Tó bá rí bẹ́ẹ̀, ẹ jẹ́ ká lọ bá a lẹ́yìn ibùdó, ká ru ẹ̀gàn tó rù,+ 14 torí a ò ní ìlú kan níbí tó ṣì máa wà, àmọ́ à ń fi gbogbo ọkàn wá èyí tó ń bọ̀.+ 15 Ẹ jẹ́ ká máa rú ẹbọ ìyìn sí Ọlọ́run nípasẹ̀ rẹ̀ nígbà gbogbo,+ ìyẹn èso ètè wa+ tó ń kéde orúkọ rẹ̀ ní gbangba.+ 16 Bákan náà, ẹ má gbàgbé láti máa ṣe rere, kí ẹ sì máa pín ohun tí ẹ ní pẹ̀lú àwọn ẹlòmíì,+ torí inú Ọlọ́run máa ń dùn gan-an sí irú àwọn ẹbọ bẹ́ẹ̀.+

17 Ẹ máa ṣègbọràn sí àwọn tó ń mú ipò iwájú láàárín yín,+ kí ẹ sì máa tẹrí ba,+ torí wọ́n ń ṣọ́ ẹ̀ṣọ́ lórí yín* bí àwọn tó máa jíhìn,+ kí wọ́n lè ṣe é tayọ̀tayọ̀, kì í ṣe pẹ̀lú ẹ̀dùn ọkàn, torí èyí máa pa yín lára.

18 Ẹ túbọ̀ máa gbàdúrà fún wa, torí ó dá wa lójú pé a ní ẹ̀rí ọkàn rere,* bó ṣe ń wù wá láti jẹ́ olóòótọ́ nínú ohun gbogbo.+ 19 Àmọ́ ní pàtàkì, mo rọ̀ yín pé kí ẹ máa gbàdúrà, kí n lè tètè pa dà sọ́dọ̀ yín.

20 Kí Ọlọ́run àlàáfíà, tó jí Jésù Olúwa wa dìde, olùṣọ́ àgùntàn ńlá+ fún àwọn àgùntàn, pẹ̀lú ẹ̀jẹ̀ májẹ̀mú àìnípẹ̀kun, 21 fi gbogbo ohun rere mú yín gbára dì láti ṣe ìfẹ́ rẹ̀, kí ó máa ṣe ohun tó dáa gan-an nínú wa lójú rẹ̀ nípasẹ̀ Jésù Kristi, ẹni tí ògo jẹ́ tiẹ̀ títí láé àti láéláé. Àmín.

22 Ẹ̀yin ará, mò ń rọ̀ yín pé kí ẹ fara balẹ̀ tẹ́tí sí ọ̀rọ̀ ìṣírí yìí, torí lẹ́tà kúkúrú ni mo kọ sí yín. 23 Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ pé wọ́n ti tú Tímótì arákùnrin wa sílẹ̀. Tó bá tètè dé, a jọ máa wá nígbà tí mo bá fẹ́ wá rí yín.

24 Ẹ bá mi kí gbogbo àwọn tó ń mú ipò iwájú láàárín yín àti gbogbo àwọn ẹni mímọ́. Àwọn tó wà ní Ítálì+ kí yín.

25 Kí inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí wà pẹ̀lú gbogbo yín.

Tàbí “àwọn àsìkò.” Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.

Tàbí “forí balẹ̀.”

Tàbí “ìránṣẹ́ rẹ̀ sí gbogbo èèyàn.”

Tàbí “ìdájọ́ òdodo.”

Tàbí “iṣẹ́ ìsìn gbogbo èèyàn.”

Tàbí “àwọn àmì.”

Wo Àfikún A5.

Tàbí “sọ àwọn tí ìbẹ̀rù ikú ti mú lẹ́rú di òmìnira.”

Ní Grk., “èso.”

Tàbí “ṣe ètùtù; rú ẹbọ láti pẹ̀tù.”

Tàbí “ìkésíni.”

Tàbí “tí a jẹ́wọ́ rẹ̀.”

Ìyẹn, Jésù.

Tàbí “ẹlẹ́rìí.”

Tàbí “jẹ́ alábàápín pẹ̀lú Kristi.”

Ní Grk., “ẹ jẹ́ ká máa bẹ̀rù.”

Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.

Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.

Tàbí “Ó lè fi sùúrù (ìwọ̀ntúnwọ̀nsì) bá àwọn aláìmọ̀kan lò.”

Tàbí “oníwàkiwà.”

Tàbí “àìlera tiẹ̀ náà ń nípa lórí rẹ̀.”

Ní Grk., “Ní àwọn ọjọ́ Kristi nínú ẹran ara.”

Tàbí “ẹ ti yigbì ní gbígbọ́.”

Ní Grk., “níbi tí àkókò dé yìí.”

Tàbí “ìwòye.”

Tàbí “àsìkò tó ń bọ̀.” Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.

Tàbí “mọ́ òpó igi.” Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.

Tàbí “pé ìpinnu òun.”

Tàbí “ó mú ìbúra kan wọ̀ ọ́.” Ní Grk., “ó fi ìbúra kan ṣe alárinà.”

Tàbí “fún ẹ̀mí wa.”

Ní Grk., “pín ìdá mẹ́wàá gbogbo nǹkan fún un.”

Tàbí “títí lọ gbére.”

Tàbí “baba ńlá.”

Ní Grk., “jáde láti abẹ́nú.”

Ní Grk., “torí ó ṣì wà ní abẹ́nú.”

Wo Àfikún A5.

Tàbí “yí ìpinnu rẹ̀ pa dà.”

Tàbí “ẹni tí a fi ṣe ìdúró májẹ̀mú tó dáa jù.”

Tàbí “ìránṣẹ́ gbogbo èèyàn.”

Wo Àfikún A5.

Tàbí “iṣẹ́ ìsìn gbogbo èèyàn.”

Wo Àfikún A5.

Wo Àfikún A5.

Wo Àfikún A5.

Wo Àfikún A5.

Tàbí “búrẹ́dì àfihàn.”

Tàbí “ibi ìpẹ̀tù.”

Ní Grk., “oríṣiríṣi ìbatisí.”

Ní Grk., “ìràpadà.”

Tàbí “abo ọmọ màlúù.”

Ní Grk., “kò ṣeé fi lọ́lẹ̀.”

Tàbí “àkájọ ìwé.”

Tàbí “iṣẹ́ ìsìn gbogbo èèyàn.”

Ní Grk., “níwájú ojú.”

Tàbí “àwọn àsìkò.” Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.

Tàbí “ohun tó yàtọ̀ sí ẹ̀ṣẹ̀ ló máa torí rẹ̀ wá.”

Tàbí kó jẹ́, “àwọn èèyàn kò lè.”

Ní Grk., “àkájọ ìwé inú ìwé náà.”

Tàbí “iṣẹ́ ìsìn gbogbo èèyàn.”

Wo Àfikún A5.

Tàbí “ìdánilójú.”

Ní Grk., “tó fi lọ́lẹ̀.”

Ní Grk., “ká di ìkéde ìrètí wa ní gbangba mú ṣinṣin.”

Tàbí “kí ọ̀rọ̀ ara wa jẹ wá lógún; kíyè sí ara wa.”

Tàbí “máa mú kó wù wá; máa ru ara wa sókè.”

Wo Àfikún A5.

Ní Grk., “síta bíi ti gbọ̀ngàn ìwòran.”

Tàbí “ẹ máa ń dúró ti.”

Ní Grk., “òmìnira yín láti sọ̀rọ̀ fàlàlà.”

Tàbí “ọkàn mi.”

Tàbí “ọkàn.”

Tàbí “ìfojúsọ́nà tó dájú nípa.”

Tàbí “ẹ̀rí tó ṣe kedere.”

Tàbí “àwọn baba ńlá wa.”

Tàbí “àwọn àsìkò.” Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.

Tàbí “jẹ́rìí nípa títẹ́wọ́ gba.”

Tàbí “jẹ́ ayàwòrán rẹ̀.”

Ní Grk., “èso.”

Tàbí “ẹni tó ṣeé gbẹ́kẹ̀ lé.”

Tàbí “àtìpó.”

Ní Grk., “èso.”

Tàbí “pàṣẹ fún wọn.”

Tàbí “nípa ìsìnkú rẹ̀.”

Ní Grk., “fọwọ́ kan àwọn àkọ́bí wọn.”

Tàbí “sọ́tọ̀ọ̀tọ̀.”

Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.

Tàbí “rẹ̀wẹ̀sì nínú ọkàn yín.”

Wo Àfikún A5.

Wo Àfikún A5.

Tàbí “bá wí.”

Tàbí “gba ìdálẹ́kọ̀ọ́.”

Ní Grk., “àwọn baba tó ni ẹran ara wa.”

Tàbí “kó ẹ̀dùn ọkàn báni.”

Tàbí “ìjẹ́mímọ́.”

Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀, “Ìṣekúṣe.”

Ìyẹn, láti yí bàbá rẹ̀ lérò pa dà.

Ní Grk., “kò rí àyè fún un.”

Tàbí “àwọsánmà.”

Tàbí “ẹgbẹẹgbàárùn-ún.”

Tàbí “wá àwáwí fún.”

Tàbí “ẹ ò ṣàìka ẹni tó ń sọ̀rọ̀ sí.”

Tàbí “ṣe inúure sí àwọn àjèjì.”

Ní Grk., “àwọn tí a dè; àwọn tó wà nínú ìdè.”

Tàbí kó jẹ́, “bí ẹni pé ẹ jọ ń jìyà.”

Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀, “Ìṣekúṣe.”

Wo Àfikún A5.

Ìyẹn, àwọn òfin nípa oúnjẹ.

Tàbí “nítòsí ẹnubodè.”

Tàbí “ọkàn yín.”

Tàbí “aláìlábòsí.”

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́