SÍ ÀWỌN ARÁ RÓÒMÙ
1 Pọ́ọ̀lù, ẹrú Kristi Jésù, tí a pè láti jẹ́ àpọ́sítélì, tí a yà sọ́tọ̀ fún ìhìn rere Ọlọ́run,+ 2 èyí tí òun ti ṣèlérí ṣáájú nípasẹ̀ àwọn wòlíì rẹ̀ nínú Ìwé Mímọ́, 3 nípa Ọmọ rẹ̀, tó jáde wá látinú ọmọ* Dáfídì+ nípa ti ara, 4 àmọ́ tí a kéde rẹ̀ ní Ọmọ Ọlọ́run+ pẹ̀lú agbára ẹ̀mí mímọ́ nípasẹ̀ àjíǹde láti inú ikú,+ bẹ́ẹ̀ ni, Jésù Kristi Olúwa wa. 5 Ipasẹ̀ rẹ̀ ni a fi rí inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí àti iṣẹ́ àpọ́sítélì+ gbà, kí a lè máa ṣègbọràn nípasẹ̀ ìgbàgbọ́ láàárín gbogbo orílẹ̀-èdè+ nítorí orúkọ rẹ̀, 6 láàárín àwọn orílẹ̀-èdè tí a ti pe ẹ̀yin náà láti di ti Jésù Kristi— 7 sí gbogbo àwọn tó wà ní Róòmù tí wọ́n jẹ́ ẹni ọ̀wọ́n fún Ọlọ́run, tí a sì pè láti jẹ́ ẹni mímọ́:
Kí inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí àti àlàáfíà láti ọ̀dọ̀ Baba wa Ọlọ́run àti Jésù Kristi Olúwa, wà pẹ̀lú yín.
8 Lákọ̀ọ́kọ́ ná, mo dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run mi nípasẹ̀ Jésù Kristi lórí gbogbo yín, torí wọ́n ń sọ̀rọ̀ nípa ìgbàgbọ́ yín káàkiri ayé. 9 Nítorí Ọlọ́run, ẹni tí mò ń fi ẹ̀mí mi ṣe iṣẹ́ ìsìn mímọ́ fún bí mo ṣe ń kéde ìhìn rere nípa Ọmọ rẹ̀, ni ẹlẹ́rìí mi bí mi ò ṣe ṣíwọ́ dídárúkọ yín nínú àdúrà mi nígbà gbogbo,+ 10 tí mò ń bẹ̀bẹ̀ pé tó bá ṣeé ṣe, kí n lè wá sọ́dọ̀ yín lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn tó bá jẹ́ ìfẹ́ Ọlọ́run. 11 Nítorí àárò yín ń sọ mí, kí n lè fún yín ní ẹ̀bùn ẹ̀mí, kí ẹ lè fìdí múlẹ̀; 12 àbí, ká kúkú sọ pé, ká jọ fún ara wa ní ìṣírí+ nípasẹ̀ ìgbàgbọ́ ẹnì kọ̀ọ̀kan wa, tiyín àti tèmi.
13 Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀, ẹ̀yin ará, pé ọ̀pọ̀ ìgbà ni mo ti fẹ́ wá sọ́dọ̀ yín, àmọ́ a ò gbà mí láyè títí di báyìí, kí iṣẹ́ ìwàásù mi lè so èso rere láàárín yín bó ṣe rí láàárín àwọn orílẹ̀-èdè tó kù. 14 Mo jẹ́ ajigbèsè sí àwọn Gíríìkì àti àwọn àjèjì,* sí àwọn ọlọ́gbọ́n àti àwọn òmùgọ̀; 15 nítorí náà, ara mi wà lọ́nà láti kéde ìhìn rere fún ẹ̀yin tí ẹ wà ní Róòmù pẹ̀lú.+ 16 Nítorí ìhìn rere kò tì mí lójú;+ ní tòótọ́, ó jẹ́ agbára Ọlọ́run tó ń mú kí gbogbo ẹni tó ní ìgbàgbọ́ rí ìgbàlà,+ àwọn Júù lákọ̀ọ́kọ́,+ lẹ́yìn náà àwọn Gíríìkì.+ 17 Nítorí inú rẹ̀ ni a ti ń fi òdodo Ọlọ́run hàn nípasẹ̀ ìgbàgbọ́ àti fún ìgbàgbọ́,+ gẹ́gẹ́ bó ṣe wà lákọsílẹ̀ pé: “Àmọ́ ìgbàgbọ́ yóò mú kí olódodo wà láàyè.”+
18 Nítorí ìrunú Ọlọ́run+ ni à ń fi hàn láti ọ̀run sí gbogbo àìṣèfẹ́ Ọlọ́run àti àìṣòdodo àwọn èèyàn tí wọ́n ń tẹ òtítọ́ rì+ ní ọ̀nà àìṣòdodo, 19 torí pé ohun tó ṣeé mọ̀ nípa Ọlọ́run fara hàn kedere láàárín wọn, nítorí Ọlọ́run mú kó ṣe kedere sí wọn.+ 20 Nítorí àwọn ànímọ́* rẹ̀ tí kò ṣeé fojú rí ni a rí ní kedere láti ìgbà ìṣẹ̀dá ayé síwájú, torí à ń fi òye mọ̀ wọ́n látinú àwọn ohun tó dá,+ títí kan agbára ayérayé tó ní+ àti bó ṣe jẹ́ Ọlọ́run,+ tó fi jẹ́ pé wọn ò ní àwíjàre. 21 Nítorí bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n mọ Ọlọ́run, wọn ò yìn ín lógo bí Ọlọ́run, bẹ́ẹ̀ ni wọn ò dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀, ìrònú wọn ò mọ́gbọ́n dání, ọkàn wọn tó ti kú tipiri sì ṣókùnkùn.+ 22 Bí wọ́n tiẹ̀ ń sọ pé àwọn jẹ́ ọlọ́gbọ́n, wọ́n ya òmùgọ̀, 23 wọ́n sì yí ògo Ọlọ́run tí kò lè díbàjẹ́ pa dà sí ohun tó dà bí àwòrán èèyàn tó lè díbàjẹ́ àti àwọn ẹyẹ àti àwọn ẹ̀dá ẹlẹ́sẹ̀ mẹ́rin pẹ̀lú àwọn ẹran tó ń fàyà fà.*+
24 Torí náà, Ọlọ́run fi wọ́n sílẹ̀ fún ìwà àìmọ́, kí wọ́n lè máa ṣe ìfẹ́ ọkàn wọn, kí wọ́n sì tàbùkù sí ẹran ara wọn. 25 Wọ́n fi irọ́ pààrọ̀ òtítọ́ Ọlọ́run, wọ́n wá ń júbà,* wọ́n sì ń ṣe iṣẹ́ ìsìn mímọ́ fún ẹ̀dá dípò Ẹlẹ́dàá, ẹni tí àwọn èèyàn ń yìn títí láé. Àmín. 26 Ìdí nìyẹn tí Ọlọ́run fi yọ̀ǹda wọn fún ìfẹ́ ìbálòpọ̀ tó ń tini lójú,+ nítorí àwọn obìnrin wọn ti yí ìlò ara wọn pa dà sí èyí tó lòdì sí ti ẹ̀dá;+ 27 bákan náà, àwọn ọkùnrin fi ìlò obìnrin* lọ́nà ti ẹ̀dá sílẹ̀, wọ́n sì jẹ́ kí ìfẹ́ ìbálòpọ̀ mú ara wọn gbóná janjan sí ara wọn, ọkùnrin sí ọkùnrin,+ wọ́n ń ṣe ohun ìbàjẹ́, wọ́n sì ń jẹ ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìyà* tó yẹ ìṣìnà wọn.+
28 Bí wọn ò ṣe gbà pé ó yẹ kí àwọn ka Ọlọ́run sí,* Ọlọ́run yọ̀ǹda wọn fún èrò orí tí kò ní ìtẹ́wọ́gbà, láti máa ṣe àwọn ohun tí kò yẹ.+ 29 Ọwọ́ wọn wá kún fún gbogbo àìṣòdodo,+ ìwà ìkà, ojúkòkòrò,*+ ìwà búburú, wọ́n kún fún owú,+ ìpànìyàn,+ wàhálà, ẹ̀tàn,+ èrò ibi,+ wọ́n jẹ́ olófòófó,* 30 ẹni tó ń sọ̀rọ̀ ẹni láìdáa,+ ẹni tó kórìíra Ọlọ́run, aláfojúdi, agbéraga, afọ́nnu, ẹni tó ń pète ohun búburú,* aṣàìgbọràn sí òbí,+ 31 aláìlóye,+ olùyẹ àdéhùn, aláìní ìfẹ́ àdámọ́ni àti aláìláàánú. 32 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn yìí mọ àṣẹ òdodo Ọlọ́run dáadáa, pé ikú tọ́ sí àwọn tó ń ṣe irú nǹkan bẹ́ẹ̀,+ kì í ṣe pé wọn ò jáwọ́ nínú àwọn ìwà yẹn nìkan ni, àmọ́ wọ́n tún ń gbóṣùbà fún àwọn tó ń ṣe wọ́n.
2 Nítorí náà, ìwọ èèyàn, o ò ní àwíjàre, ẹni tó wù kí o jẹ́,+ tí o bá ṣèdájọ́; torí nígbà tí o bá ṣèdájọ́ ẹlòmíì, ara rẹ lò ń dá lẹ́bi, nítorí ìwọ tí ò ń ṣèdájọ́ ń ṣe ohun kan náà.+ 2 Tóò, a mọ̀ pé ìdájọ́ Ọlọ́run bá òtítọ́ mu, ó sì dẹ́bi fún àwọn tó ń ṣe irú àwọn nǹkan yìí.
3 Àmọ́, ìwọ èèyàn, ṣé o rò pé wàá bọ́ nínú ìdájọ́ Ọlọ́run bí o ṣe ń ṣèdájọ́ àwọn tó ń ṣe irú àwọn nǹkan yìí, síbẹ̀ tí ìwọ fúnra rẹ ń ṣe wọ́n? 4 Àbí ṣé o fojú kéré ọlá inú rere rẹ̀+ àti ìmúmọ́ra*+ pẹ̀lú sùúrù rẹ̀,+ torí o ò mọ̀ pé Ọlọ́run, nínú inú rere rẹ̀, fẹ́ darí rẹ sí ìrònúpìwàdà?+ 5 Àmọ́ nítorí agídí rẹ àti ọkàn rẹ tí kò ronú pìwà dà, ò ń kó ìrunú jọ sórí ara rẹ, ìrunú yìí máa hàn ní ọjọ́ ìdájọ́ òdodo Ọlọ́run.+ 6 Yóò san kálukú lẹ́san gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀:+ 7 ìyè àìnípẹ̀kun fún àwọn tó ń wá ògo àti ọlá àti àìlèdíbàjẹ́+ nípasẹ̀ ìfaradà nínú iṣẹ́ rere; 8 àmọ́, fún àwọn tó jẹ́ alárìíyànjiyàn, tí wọ́n ń ṣàìgbọràn sí òtítọ́, tí wọ́n sì ń ṣègbọràn sí àìṣòdodo, ìrunú àti ìbínú yóò wá sórí wọn.+ 9 Ìpọ́njú àti wàhálà yóò wà lórí gbogbo ẹni* tó ń ṣe ohun aṣeniléṣe, lórí Júù lákọ̀ọ́kọ́ àti lórí Gíríìkì pẹ̀lú; 10 àmọ́ ògo àti ọlá àti àlàáfíà yóò wà fún gbogbo ẹni tó ń ṣe rere, fún Júù lákọ̀ọ́kọ́ + àti fún Gíríìkì pẹ̀lú.+ 11 Nítorí kò sí ojúsàájú lọ́dọ̀ Ọlọ́run.+
12 Nítorí gbogbo àwọn tó ṣẹ̀ láìsí òfin á ṣègbé láìsí òfin;+ àmọ́ gbogbo àwọn tó ṣẹ̀ lábẹ́ òfin ni a ó fi òfin dá lẹ́jọ́.+ 13 Nítorí kì í ṣe àwọn tó ń gbọ́ òfin ni olódodo níwájú Ọlọ́run, àmọ́ àwọn tó ń ṣe ohun tí òfin sọ ni a ó pè ní olódodo.+ 14 Torí nígbà tí àwọn èèyàn orílẹ̀-èdè tí kò ní òfin+ bá ṣe àwọn ohun tó jẹ́ ti òfin lọ́nà ti ẹ̀dá, bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọn ò ní òfin, àwọn èèyàn yìí jẹ́ òfin fún ara wọn. 15 Àwọn gan-an ló ń ṣe ohun tó fi hàn pé a kọ òfin sínú ọkàn wọn, bí ẹ̀rí ọkàn wọn ṣe ń jẹ́ wọn lẹ́rìí, tí ìrònú wọn sì ń* fẹ̀sùn kàn wọ́n tàbí dá wọn láre. 16 Èyí á ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ tí Ọlọ́run máa ṣèdájọ́ ohun ìkọ̀kọ̀ aráyé+ nípasẹ̀ Kristi Jésù, gẹ́gẹ́ bí ìhìn rere tí mò ń kéde.
17 Tí wọ́n bá ń pè ẹ́ ní Júù,+ tí o gbára lé òfin, tí o sì ń fi Ọlọ́run yangàn, 18 tí o mọ ìfẹ́ rẹ̀, tí o sì fara mọ́ àwọn ohun títayọ lọ́lá nítorí a ti kọ́ ẹ* látinú Òfin,+ 19 tí o sì gbà pé o jẹ́ afinimọ̀nà fún àwọn afọ́jú, ìmọ́lẹ̀ fún àwọn tó wà nínú òkùnkùn, 20 ẹni tó ń tọ́ àwọn aláìnírònú sọ́nà, olùkọ́ àwọn ọmọdé, tí o sì lóye ìpìlẹ̀ ìmọ̀ àti ti òtítọ́ inú Òfin— 21 àmọ́, ṣé ìwọ tó ń kọ́ ẹlòmíì ti kọ́ ara rẹ?+ Ìwọ tí ò ń wàásù pé, “Má jalè,”+ ṣé o kì í jalè? 22 Ìwọ tí ò ń sọ pé “Má ṣe àgbèrè,”+ ṣé o kì í ṣe àgbèrè? Ìwọ tí o kórìíra àwọn òrìṣà, ṣé o kì í ja tẹ́ńpìlì lólè? 23 Ìwọ tí ò ń fi òfin yangàn, ṣé o kì í tàbùkù sí Ọlọ́run nípa rírú Òfin? 24 Torí “àwọn èèyàn ń sọ̀rọ̀ òdì sí orúkọ Ọlọ́run láàárín àwọn orílẹ̀-èdè nítorí yín,” bó ṣe wà lákọsílẹ̀.+
25 Ìdádọ̀dọ́*+ ṣàǹfààní lóòótọ́ kìkì tí o bá ń ṣe ohun tí òfin sọ;+ àmọ́ tí o bá jẹ́ arúfin, ìdádọ̀dọ́* rẹ ti di àìdádọ̀dọ́.* 26 Nítorí náà, tí aláìdádọ̀dọ́*+ bá ń pa ohun òdodo tí Òfin sọ mọ́, a ó ka àìdádọ̀dọ́* rẹ̀ sí ìdádọ̀dọ́,* àbí bẹ́ẹ̀ kọ́?+ 27 Ẹni tó jẹ́ aláìdádọ̀dọ́* nípa tara yóò fi pípa Òfin mọ́ ṣèdájọ́ ìwọ tó jẹ́ arúfin, láìka pé o ní àkọsílẹ̀ òfin, o sì dádọ̀dọ́.* 28 Nítorí ẹni tó jẹ́ Júù ní òde kì í ṣe Júù,+ bẹ́ẹ̀ ni ìdádọ̀dọ́* kì í ṣe ohun tó wà ní òde ara.+ 29 Àmọ́ ẹni tó jẹ́ Júù ní inú ni Júù,+ ìdádọ̀dọ́* rẹ̀ sì jẹ́ ti ọkàn+ nípa ẹ̀mí, kì í ṣe nípa àkọsílẹ̀ òfin.+ Ọ̀dọ̀ Ọlọ́run ni ìyìn ẹni yẹn ti wá, kì í ṣe láti ọ̀dọ̀ èèyàn.+
3 Kí wá làǹfààní àwọn Júù tàbí kí làǹfààní ìdádọ̀dọ́?* 2 Ó pọ̀ gan-an ní gbogbo ọ̀nà. Lákọ̀ọ́kọ́ ná, ìkáwọ́ wọn la fi àwọn ọ̀rọ̀ ìkéde mímọ́ Ọlọ́run sí.+ 3 Kí ló máa wá ṣẹlẹ̀ tí àwọn kan ò bá ní ìgbàgbọ́? Ṣé àìnígbàgbọ́ wọn máa mú kí àwọn èèyàn má gba ọ̀rọ̀ Ọlọ́run gbọ́ mọ́ ni? 4 Ká má ri! Àmọ́ kí Ọlọ́run jẹ́ olóòótọ́,+ kódà bí gbogbo èèyàn bá tiẹ̀ jẹ́ òpùrọ́,+ bó ṣe wà lákọsílẹ̀ pé: “Kí àwọn ọ̀rọ̀ rẹ lè fi ọ́ hàn ní olódodo, kí o sì lè jàre ẹjọ́ rẹ.”+ 5 Àmọ́, kí ni ká sọ bí àìṣòdodo wa bá gbé òdodo Ọlọ́run yọ? Ọlọ́run kì í ṣe aláìṣẹ̀tọ́ nígbà tó bá tú ìrunú rẹ̀ jáde, àbí? (Mò ń sọ̀rọ̀ bí èèyàn ni o.) 6 Ká má ri! Tó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀ ni, báwo ni Ọlọ́run ṣe máa ṣèdájọ́ ayé?+
7 Àmọ́ tó bá jẹ́ pé torí irọ́ mi ni òtítọ́ Ọlọ́run fi túbọ̀ fara hàn láti gbé ògo rẹ̀ yọ, kí ló dé tí a tún fi ń ṣèdájọ́ mi bí ẹlẹ́ṣẹ̀? 8 A ò ṣe kúkú wá sọ bí àwọn kan ṣe ń parọ́ mọ́ wa tí wọ́n ní a sọ pé, “Ẹ jẹ́ ká ṣe àwọn ohun búburú kí àwọn ohun rere lè jáde wá”? Ìdájọ́ àwọn èèyàn yìí bá ìdájọ́ òdodo mu.+
9 Kí wá ni? Ṣé a sàn jù wọ́n lọ ni? Rárá o! Torí a ti sọ ọ́ níṣàájú pé gbogbo àwọn Júù àti àwọn Gíríìkì wà lábẹ́ ẹ̀ṣẹ̀;+ 10 bó ṣe wà lákọsílẹ̀ pé: “Kò sí olódodo kankan, kò tiẹ̀ sí ẹyọ kan;+ 11 kò sí ẹnì kankan tó ní ìjìnlẹ̀ òye; kò sí ẹni tó ń wá Ọlọ́run. 12 Gbogbo èèyàn ti fi ọ̀nà sílẹ̀, gbogbo wọn ti di aláìníláárí; kò sí ẹnì kankan tó ń ṣoore, kò tiẹ̀ sí ẹyọ kan.”+ 13 “Sàréè tó ṣí sílẹ̀ ni ọ̀fun wọn, wọ́n ti fi ahọ́n wọn tanni jẹ.”+ “Oró paramọ́lẹ̀* wà lábẹ́ ètè wọn.”+ 14 “Ègún àti ọ̀rọ̀ kíkorò ló kún ẹnu wọn.”+ 15 “Ẹsẹ̀ wọn yá nílẹ̀ láti ta ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀.”+ 16 “Ìparun àti ìyà wà ní àwọn ọ̀nà wọn, 17 wọn kò sì mọ ọ̀nà àlàáfíà.”+ 18 “Kò sí ìbẹ̀rù Ọlọ́run lójú wọn.”+
19 A mọ̀ pé gbogbo nǹkan tí Òfin sọ ló wà fún àwọn tó wà lábẹ́ Òfin, kí a lè pa gbogbo èèyàn lẹ́nu mọ́, kí gbogbo ayé sì lè yẹ fún ìyà lọ́dọ̀ Ọlọ́run.+ 20 Nítorí náà, kò sí ẹni* tí a máa pè ní olódodo níwájú rẹ̀ nípasẹ̀ àwọn iṣẹ́ òfin,+ torí òfin ló jẹ́ ká ní ìmọ̀ pípéye nípa ẹ̀ṣẹ̀.+
21 Àmọ́ ní báyìí, láìgbára lé òfin, a ti fi òdodo Ọlọ́run hàn,+ bí Òfin àti àwọn Wòlíì ṣe jẹ́rìí sí i,+ 22 bẹ́ẹ̀ ni, òdodo Ọlọ́run nípasẹ̀ ìgbàgbọ́ nínú Jésù Kristi, tó wà fún gbogbo àwọn tó ní ìgbàgbọ́. Nítorí kò sí ìyàtọ̀.+ 23 Torí gbogbo èèyàn ti ṣẹ̀, wọn ò sì kúnjú ìwọ̀n ògo Ọlọ́run,+ 24 bí a ṣe pè wọ́n ní olódodo dà bí ẹ̀bùn ọ̀fẹ́+ tí wọ́n rí gbà nípasẹ̀ inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí rẹ̀,+ èyí tó wá nípasẹ̀ ìtúsílẹ̀ tí ìràpadà tí Kristi Jésù san mú kó ṣeé ṣe.+ 25 Ọlọ́run fi í lélẹ̀ láti jẹ́ ẹbọ ìpẹ̀tù*+ nípasẹ̀ ìgbàgbọ́ nínú ẹ̀jẹ̀ rẹ̀.+ Kí ó lè fi òdodo rẹ̀ hàn, torí Ọlọ́run, nínú ìmúmọ́ra* rẹ̀, ń dárí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tó wáyé nígbà àtijọ́ jini. 26 Èyí jẹ́ láti fi òdodo rẹ̀+ hàn ní àsìkò yìí, kí ó lè jẹ́ olódodo kódà nígbà tó bá ń pe èèyàn tó ní ìgbàgbọ́ nínú Jésù ní olódodo.+
27 Kí ló wá fa ìyangàn? Kò sáyè fún ìyẹn. Nípasẹ̀ òfin wo? Ṣé ti iṣẹ́ ni?+ Rárá o, àmọ́ nípasẹ̀ òfin ìgbàgbọ́. 28 Nítorí a gbà pé ìgbàgbọ́ ló ń mú kí a pe èèyàn kan ní olódodo kì í ṣe àwọn iṣẹ́ òfin.+ 29 Àbí ṣé Ọlọ́run àwọn Júù nìkan ni?+ Ṣé kì í ṣe Ọlọ́run àwọn èèyàn orílẹ̀-èdè pẹ̀lú?+ Bẹ́ẹ̀ ni, òun náà ni Ọlọ́run àwọn èèyàn orílẹ̀-èdè.+ 30 Nítorí ọ̀kan ni Ọlọ́run,+ ó máa pe àwọn tó dádọ̀dọ́* ní olódodo + nítorí ìgbàgbọ́, á sì pe àwọn aláìdádọ̀dọ́* ní olódodo + nípasẹ̀ ìgbàgbọ́ wọn. 31 Ṣé a wá pa òfin rẹ́ nípasẹ̀ ìgbàgbọ́ wa ni? Rárá o! Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe la fìdí òfin múlẹ̀.+
4 Tí ọ̀rọ̀ bá rí bẹ́ẹ̀, kí la lè sọ pé ó jẹ́ èrè Ábúráhámù, baba ńlá wa nípa ti ara? 2 Bí àpẹẹrẹ, tó bá jẹ́ àwọn iṣẹ́ ló mú ká pe Ábúráhámù ní olódodo, yóò ní ìdí láti yangàn, àmọ́ kì í ṣe níwájú Ọlọ́run. 3 Kí ni ìwé mímọ́ sọ? “Ábúráhámù ní ìgbàgbọ́ nínú Jèhófà,* ó sì kà á sí òdodo fún un.”+ 4 Lójú ẹni tó ń ṣiṣẹ́, kì í ka owó iṣẹ́ rẹ̀ sí inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí, gbèsè* tí wọ́n jẹ ẹ́ ló máa kà á sí. 5 Ṣùgbọ́n lójú ẹni tí kò ṣiṣẹ́, àmọ́ tó ní ìgbàgbọ́ nínú Ẹni tó ń pe àwọn tí kò ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run ní olódodo, ìgbàgbọ́ rẹ̀ ni a kà sí òdodo.+ 6 Bí Dáfídì pẹ̀lú ṣe sọ nípa ayọ̀ ẹni tí Ọlọ́run kà sí olódodo láìka àwọn iṣẹ́ rẹ̀ sí, pé: 7 “Aláyọ̀ ni àwọn tí a dárí ìwà wọn tí kò bófin mu jì, tí a sì bo ẹ̀ṣẹ̀ wọn mọ́lẹ̀;* 8 aláyọ̀ ni ẹni tí Jèhófà* kò ka ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ sí lọ́rùn lọ́nàkọnà.”+
9 Ṣé àwọn tó dádọ̀dọ́* nìkan ni ayọ̀ yìí wà fún ni, ṣé kò dé ọ̀dọ̀ àwọn aláìdádọ̀dọ́* pẹ̀lú ni?+ Nítorí a sọ pé: “Ìgbàgbọ́ Ábúráhámù ló mú ká kà á sí olódodo.”+ 10 Lábẹ́ ipò wo ni a ti wá pè é ní olódodo? Ṣé ìgbà tó ti dádọ̀dọ́* ni àbí ìgbà tí kò tíì dádọ̀dọ́? Kó tó dádọ̀dọ́ ni, ó ṣì jẹ́ aláìdádọ̀dọ́.* 11 Ó gba àmì kan,+ ìyẹn, ìdádọ̀dọ́,* gẹ́gẹ́ bí èdìdì* òdodo nípasẹ̀ ìgbàgbọ́ tó ní nígbà tó ṣì jẹ́ aláìdádọ̀dọ́,* kí ó lè jẹ́ baba gbogbo àwọn tó ní ìgbàgbọ́+ nígbà tí wọ́n ṣì jẹ́ aláìdádọ̀dọ́, kí a lè kà wọ́n sí olódodo; 12 kí ó sì tún lè jẹ́ baba àwọn ọmọ tó ti dádọ̀dọ́,* kì í ṣe ti àwọn tó rọ̀ mọ́ ìdádọ̀dọ́* nìkan, àmọ́ ó tún jẹ́ baba àwọn tó ń rìn létòlétò nínú ìgbàgbọ́ tí baba wa Ábúráhámù+ ní nígbà tó ṣì jẹ́ aláìdádọ̀dọ́.*
13 Kì í ṣe nípasẹ̀ òfin ni Ábúráhámù tàbí ọmọ* rẹ̀ fi gba ìlérí pé òun ló máa jẹ́ ajogún ayé,+ àmọ́ ó jẹ́ nípasẹ̀ òdodo tó wá látinú ìgbàgbọ́.+ 14 Nítorí tó bá jẹ́ àwọn tó rọ̀ mọ́ òfin ni ajogún, ìgbàgbọ́ ò wúlò nìyẹn, ìlérí náà á sì di òtúbáńtẹ́. 15 Ní ti gidi, Òfin ń mú ìrunú wá,+ àmọ́ níbi tí kò bá sí òfin, kò sí ẹ̀ṣẹ̀.+
16 Ìdí nìyẹn tí ìlérí náà fi jẹ́ nípasẹ̀ ìgbàgbọ́, kó lè jẹ́ nípa inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí,+ kí ìlérí náà lè ṣẹ fún gbogbo ọmọ* rẹ̀,+ kì í ṣe fún àwọn tó rọ̀ mọ́ Òfin nìkan, àmọ́ kí ó lè ṣẹ fún àwọn tó rọ̀ mọ́ ìgbàgbọ́ Ábúráhámù pẹ̀lú, tó jẹ́ baba gbogbo wa.+ 17 (Èyí bá ohun tó wà lákọsílẹ̀ mu pé: “Mo ti yàn ọ́ ṣe bàbá ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè.”)+ Èyí jẹ́ lójú Ọlọ́run, ẹni tó ní ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀, tó ń sọ òkú di ààyè, tó sì ń pe àwọn ohun tí kò sí bíi pé wọ́n wà.* 18 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó kọjá ohun tó ṣeé retí, síbẹ̀ lórí ìrètí, ó ní ìgbàgbọ́ pé òun máa di bàbá ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè gẹ́gẹ́ bí ohun tí a ti sọ pé: “Bí ọmọ* rẹ á ṣe pọ̀ nìyẹn.”+ 19 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìgbàgbọ́ rẹ̀ kò yẹ̀, ó ro ti ara rẹ̀ tó ti di òkú tán (torí ó ti tó nǹkan bí ẹni ọgọ́rùn-ún [100] ọdún),+ ó tún ro ti ilé ọlẹ̀ Sérà tó ti kú.*+ 20 Àmọ́ nítorí ìlérí Ọlọ́run, ó ní ìgbàgbọ́, kò sì ṣiyèméjì; ìgbàgbọ́ rẹ̀ mú kó di alágbára, ó sì ń fi ògo fún Ọlọ́run, 21 bó ṣe dá a lójú hán-ún pé Ọlọ́run lè ṣe ohun tí Ó ṣèlérí.+ 22 Nítorí náà, “a kà á sí òdodo fún un.”+
23 Àmọ́, ọ̀rọ̀ tí a kọ pé “a kà á sí” kì í ṣe nítorí rẹ̀ nìkan,+ 24 àmọ́ ó jẹ́ nítorí wa pẹ̀lú, àwa tí a máa kà sí olódodo, nítorí a nígbàgbọ́ nínú Ẹni tó gbé Jésù Olúwa wa dìde kúrò nínú ikú.+ 25 Ọlọ́run fi í lélẹ̀ nítorí àwọn àṣemáṣe wa,+ ó sì gbé e dìde kí a lè pè wá ní olódodo.+
5 Tóò, ní báyìí tí a ti pè wá ní olódodo nítorí ìgbàgbọ́,+ ẹ jẹ́ kí a máa gbádùn àlàáfíà* pẹ̀lú Ọlọ́run nípasẹ̀ Olúwa wa Jésù Kristi,+ 2 ẹni tó mú ká rí inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí tí à ń gbádùn báyìí gbà nípasẹ̀ ìgbàgbọ́;+ ẹ jẹ́ kí a máa yọ̀,* lórí ìrètí ògo Ọlọ́run. 3 Kì í ṣe ìyẹn nìkan, àmọ́ ẹ jẹ́ ká máa yọ̀* nígbà tí a bá wà nínú ìpọ́njú,+ torí a mọ̀ pé ìpọ́njú ń mú ìfaradà wá;+ 4 ìfaradà ní tirẹ̀ ń mú ìtẹ́wọ́gbà wá;+ ìtẹ́wọ́gbà sì ń mú ìrètí wá,+ 5 ìrètí kì í sì í yọrí sí ìjákulẹ̀;+ nítorí pé a ti tú ìfẹ́ Ọlọ́run jáde sínú ọkàn wa nípasẹ̀ ẹ̀mí mímọ́, èyí tí a fún wa.+
6 Torí, ní tòótọ́, nígbà tí a ṣì jẹ́ aláìlera,+ Kristi kú fún àwọn tí kò ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run ní àkókò tí a yàn. 7 Bóyá ni ẹnì kan á lè kú nítorí olódodo; síbẹ̀, ẹnì kan lè ṣe tán láti kú nítorí ẹni rere. 8 Àmọ́ Ọlọ́run dámọ̀ràn ìfẹ́ rẹ̀ fún wa ní ti pé, nígbà tí a ṣì jẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀, Kristi kú fún wa.+ 9 Nígbà tí a sì ti wá pè wá ní olódodo nípasẹ̀ ẹ̀jẹ̀ rẹ̀,+ ó dájú pé ó máa mú kí a bọ́ lọ́wọ́ ìrunú.+ 10 Torí tó bá jẹ́ pé nígbà tí a jẹ́ ọ̀tá, ikú Ọmọ Ọlọ́run mú wa pa dà bá a rẹ́,+ ǹjẹ́ ààyè rẹ̀ kò ní mú ká rí ìgbàlà ní báyìí tí a ti pa dà bá a rẹ́? 11 Kì í ṣe ìyẹn nìkan, àmọ́ a tún ń yọ̀ nínú Ọlọ́run nípasẹ̀ Olúwa wa Jésù Kristi, ẹni tó mú ká rí ìpadàrẹ́ gbà ní báyìí.+
12 Ìdí nìyẹn tó fi jẹ́ pé, bí ẹ̀ṣẹ̀ ṣe tipasẹ̀ ẹnì kan wọ ayé, tí ikú sì wá nípasẹ̀ ẹ̀ṣẹ̀,+ bẹ́ẹ̀ ni ikú ṣe tàn dé ọ̀dọ̀ gbogbo èèyàn torí pé gbogbo wọn ti dẹ́ṣẹ̀+—. 13 Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ ti wà ní ayé kí Òfin tó dé, àmọ́ a kì í ka ẹ̀ṣẹ̀ sí ẹnikẹ́ni lọ́rùn nígbà tí kò sí òfin.+ 14 Síbẹ̀, ikú jọba láti ọ̀dọ̀ Ádámù títí dé ọ̀dọ̀ Mósè, àní lórí àwọn tí kò dẹ́ṣẹ̀ bíi ti Ádámù, ẹni tó fara jọ ẹni tó ń bọ̀.+
15 Àmọ́ ẹ̀bùn náà ò rí bí àṣemáṣe. Torí bó ṣe jẹ́ pé nípa àṣemáṣe ọkùnrin kan ni ọ̀pọ̀ èèyàn fi kú, ẹ wo bí inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Ọlọ́run àti ẹ̀bùn ọ̀fẹ́ rẹ̀ nípasẹ̀ inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí ọkùnrin kan,+ ìyẹn Jésù Kristi, ṣe ṣe ọ̀pọ̀ èèyàn láǹfààní!*+ 16 Bákan náà, àǹfààní tí ẹ̀bùn ọ̀fẹ́ yìí mú wá kì í ṣe ohun kan náà pẹ̀lú ohun tí ẹ̀ṣẹ̀ ọkùnrin kan mú wá.+ Nítorí ìdájọ́ tó tẹ̀ lé àṣemáṣe kan yọrí sí ìdálẹ́bi ọ̀pọ̀ èèyàn,+ àmọ́ ẹ̀bùn tó tẹ̀ lé ọ̀pọ̀ àṣemáṣe yọrí sí pípè wọ́n ní olódodo.+ 17 Torí tí àṣemáṣe ọkùnrin kan bá mú kí ikú jọba nípasẹ̀ ẹni náà,+ ǹjẹ́ àwọn tó gba ọ̀pọ̀lọpọ̀ inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí àti ẹ̀bùn ọ̀fẹ́ òdodo+ kò ní jọba+ nínú ìyè nípasẹ̀ èèyàn kan, ìyẹn Jésù Kristi?+
18 Nítorí náà, bó ṣe jẹ́ pé àṣemáṣe kan ló yọrí sí ìdálẹ́bi onírúurú èèyàn,+ bẹ́ẹ̀ náà ló ṣe jẹ́ pé ìwà òdodo kan ló mú ká pe onírúurú èèyàn+ ní olódodo fún ìyè.+ 19 Nítorí bó ṣe jẹ́ pé àìgbọràn èèyàn kan ló mú kí ọ̀pọ̀ èèyàn di ẹlẹ́ṣẹ̀,+ bẹ́ẹ̀ náà ni ìgbọràn èèyàn kan á ṣe mú kí ọ̀pọ̀ èèyàn di olódodo.+ 20 Tóò, Òfin wọlé wá kí àṣemáṣe lè pọ̀ sí i.+ Àmọ́ níbi tí ẹ̀ṣẹ̀ bá ti pọ̀, inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí á pọ̀ jù ú lọ. 21 Nítorí kí ni? Kí ó lè jẹ́ pé bí ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú ṣe jọba,+ kí inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí lè jọba nípasẹ̀ òdodo, kí ó sì yọrí sí ìyè àìnípẹ̀kun nípasẹ̀ Jésù Kristi Olúwa wa.+
6 Kí ni ká wá sọ? Ṣé ká máa dá ẹ̀ṣẹ̀ lọ kí inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí lè máa pọ̀ sí i ni? 2 Ká má ri! Bó ṣe jẹ́ pé a ti bọ́ lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀,+ ṣé ó yẹ kó ṣì tún máa darí wa?+ 3 Àbí ẹ ò mọ̀ pé gbogbo wa tí a ti batisí sínú Kristi Jésù+ la ti batisí sínú ikú rẹ̀?+ 4 Nítorí náà, a sin wá pọ̀ pẹ̀lú rẹ̀ nípasẹ̀ ìbatisí wa sínú ikú rẹ̀,+ kí ó lè jẹ́ pé bí a ti gbé Kristi dìde kúrò nínú ikú nípasẹ̀ ògo Baba, kí àwa náà lè máa gbé ìgbé ayé ọ̀tun.+ 5 Bí a ṣe wà ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú rẹ̀ lọ́nà tó gbà kú,+ ó dájú pé a ó tún lè wà níṣọ̀kan pẹ̀lú rẹ̀ lọ́nà tó gbà jíǹde.+ 6 Torí a mọ̀ pé a ti kan ìwà wa àtijọ́ mọ́gi* pẹ̀lú rẹ̀,+ kí ara ẹ̀ṣẹ̀ wa lè di aláìlágbára,+ kí a má ṣe jẹ́ ẹrú ẹ̀ṣẹ̀ mọ́.+ 7 Nítorí ẹni tó bá ti kú ni a ti dá sílẹ̀ pátápátá* kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀.
8 Yàtọ̀ síyẹn, tí a bá ti kú pẹ̀lú Kristi, a gbà gbọ́ pé a ó tún wà láàyè pẹ̀lú rẹ̀. 9 Torí a mọ̀ pé ní báyìí tí a ti gbé Kristi dìde kúrò nínú ikú,+ kò ní kú mọ́;+ ikú kò lágbára lórí rẹ̀ mọ́. 10 Nítorí ikú tó kú jẹ́ láti mú ẹ̀ṣẹ̀ kúrò,* ó kú lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo láìtún ní kú mọ́ láé,+ àmọ́ ìgbé ayé tó ń gbé jẹ́ láti máa ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run. 11 Bákan náà, kí ẹ gbà pé ẹ ti kú nínú ẹ̀ṣẹ̀ àmọ́ ẹ wà láàyè nínú Ọlọ́run nípasẹ̀ Kristi Jésù.+
12 Nítorí náà, ẹ má ṣe jẹ́ kí ẹ̀ṣẹ̀ máa jọba lọ nínú ara kíkú yín,+ tí ẹ ó fi máa ṣe ìfẹ́ ti ara. 13 Bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ má ṣe jẹ́ kí ẹ̀ṣẹ̀ máa lo àwọn ẹ̀yà ara* yín bí ohun ìjà àìṣòdodo mọ́, àmọ́ ẹ fi ara yín fún Ọlọ́run bí àwọn tí a gbé dìde látinú ikú, kí ẹ sì fi àwọn ẹ̀yà ara* yín fún Ọlọ́run bí ohun ìjà òdodo.+ 14 Torí ẹ̀ṣẹ̀ kò gbọ́dọ̀ jẹ ọ̀gá lórí yín, nítorí ẹ ò sí lábẹ́ òfin,+ àmọ́ ẹ wà lábẹ́ inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí.+
15 Kí ló wá kàn? Ṣé ká wá máa dẹ́ṣẹ̀ torí pé a ò sí lábẹ́ òfin, àmọ́ a wà lábẹ́ inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí ni?+ Ká má ri! 16 Ṣé ẹ ò mọ̀ pé tí ẹ bá fi ara yín ṣe ẹrú tó ń ṣègbọràn fún ẹnì kan, ẹrú lẹ jẹ́ fún ẹni tí ẹ̀ ń ṣègbọràn sí,+ ì báà jẹ́ fún ẹ̀ṣẹ̀+ tó ń yọrí sí ikú+ tàbí fún ìgbọràn tó ń yọrí sí òdodo? 17 Àmọ́ ọpẹ́ ni fún Ọlọ́run pé bí ẹ tiẹ̀ jẹ́ ẹrú ẹ̀ṣẹ̀ nígbà kan rí, ẹ ti ń ṣègbọràn látọkàn wá sí ẹ̀kọ́ tí a fi lé yín lọ́wọ́. 18 Bẹ́ẹ̀ ni, àtìgbà tí a ti dá yín sílẹ̀ kúrò lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀+ ni ẹ ti di ẹrú òdodo.+ 19 Mò ń lo ọ̀rọ̀ tí èèyàn lè tètè lóye nítorí àìlera ara yín; torí bí ẹ ṣe fi àwọn ẹ̀yà ara yín ṣe ẹrú ìwà àìmọ́ àti ìwà tí kò bófin mu tó ń yọrí sí ìwà tí kò bófin mu, bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ fi àwọn ẹ̀yà ara yín ṣe ẹrú ní báyìí fún òdodo tó ń yọrí sí ìjẹ́mímọ́.+ 20 Torí nígbà tí ẹ jẹ́ ẹrú ẹ̀ṣẹ̀, ẹ ò sí lábẹ́ òdodo.
21 Kí wá ni èso tí ẹ̀ ń mú jáde nígbà yẹn? Àwọn nǹkan tó ń tì yín lójú ní báyìí. Nítorí ikú ni òpin àwọn nǹkan yẹn.+ 22 Àmọ́ ní báyìí tí a ti dá yín sílẹ̀ kúrò lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀, tí ẹ sì ti di ẹrú Ọlọ́run, ẹ̀ ń so èso yín lọ́nà ìjẹ́mímọ́,+ ìyè àìnípẹ̀kun sì ni òpin rẹ̀.+ 23 Nítorí ikú ni èrè* ẹ̀ṣẹ̀,+ àmọ́ ìyè àìnípẹ̀kun ni ẹ̀bùn tí Ọlọ́run ń fúnni+ nípasẹ̀ Kristi Jésù Olúwa wa.+
7 Ǹjẹ́ a lè sọ pé ẹ ò mọ̀, ẹ̀yin ará, (torí àwọn tó mọ òfin ni mò ń bá sọ̀rọ̀,) pé Òfin jẹ́ ọ̀gá lórí èèyàn ní gbogbo ìgbà tó bá fi wà láàyè? 2 Bí àpẹẹrẹ, òfin de obìnrin tí a gbé níyàwó mọ́ ọkọ rẹ̀ nígbà tí ọkùnrin náà bá wà láàyè; àmọ́ tí ọkọ rẹ̀ bá kú, a dá a sílẹ̀ kúrò lábẹ́ òfin ọkọ rẹ̀.+ 3 Torí náà, nígbà tí ọkọ rẹ̀ bá wà láàyè, a ó pè é ní alágbèrè obìnrin tó bá fẹ́ ọkùnrin míì.+ Àmọ́ tí ọkọ rẹ̀ bá kú, ó bọ́ lọ́wọ́ òfin rẹ̀, kì í sì í ṣe alágbèrè obìnrin tó bá fẹ́ ọkùnrin míì.+
4 Nítorí náà, ẹ̀yin ará mi, a ti sọ ẹ̀yin náà di òkú sí Òfin nípasẹ̀ ara Kristi, kí ẹ lè di ti ẹlòmíì,+ ẹni tí a gbé dìde kúrò nínú ikú,+ kí a lè máa so èso fún Ọlọ́run.+ 5 Torí nígbà tí à ń gbé lọ́nà ti ara, àwọn ìfẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ tí Òfin mú kó hàn síta ń ṣiṣẹ́ nínú ara* wa, kí ó lè mú èso ikú jáde.+ 6 Àmọ́ ní báyìí, a ti dá wa sílẹ̀ kúrò lọ́wọ́ Òfin,+ torí a ti kú sí èyí tó ń ká wa lọ́wọ́ kò tẹ́lẹ̀, kí a lè jẹ́ ẹrú ní ọ̀nà tuntun nípasẹ̀ ẹ̀mí,+ kì í sì í ṣe ní ọ̀nà àtijọ́ nípasẹ̀ àkọsílẹ̀ òfin.+
7 Kí wá ni ká sọ? Ṣé Òfin wá jẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ ni? Kò rí bẹ́ẹ̀ rárá! Ká sòótọ́, mi ò bá má ti mọ ẹ̀ṣẹ̀ tí kì í bá ṣe Òfin.+ Bí àpẹẹrẹ, mi ò bá má mọ ojúkòkòrò ká ní Òfin ò sọ pé: “O ò gbọ́dọ̀ ṣojúkòkòrò.”+ 8 Àmọ́ bí ẹ̀ṣẹ̀ ṣe rí àyè nípasẹ̀ àṣẹ, ó mú kí n máa ṣojúkòkòrò lóríṣiríṣi ọ̀nà, nítorí láìsí òfin, ẹ̀ṣẹ̀ jẹ́ òkú.+ 9 Lóòótọ́, ìgbà kan wà tí mo wà láàyè láìsí òfin. Àmọ́ nígbà tí àṣẹ dé, ẹ̀ṣẹ̀ tún sọ jí, mo sì kú.+ 10 Àṣẹ tó yẹ kó yọrí sí ìyè+ ni mo rí pé ó yọrí sí ikú. 11 Nítorí bí ẹ̀ṣẹ̀ ṣe rí àyè nípasẹ̀ àṣẹ, ó sún mi dẹ́ṣẹ̀, ó sì tipasẹ̀ rẹ̀ pa mí. 12 Torí náà, Òfin jẹ́ mímọ́ láyè ara rẹ̀, àṣẹ sì jẹ́ mímọ́, ó jẹ́ òdodo, ó sì dára.+
13 Nígbà náà, ṣé ohun tó dára ló yọrí sí ikú mi ni? Kò rí bẹ́ẹ̀ rárá! Ẹ̀ṣẹ̀ ni, kí a lè fi hàn pé ẹ̀ṣẹ̀ ló yọrí sí ikú mi nípasẹ̀ ohun tó dára,+ kó lè jẹ́ pé nípasẹ̀ àṣẹ, ẹ̀ṣẹ̀ á túbọ̀ burú sí i.+ 14 Nítorí a mọ̀ pé Òfin jẹ́ ti ẹ̀mí, àmọ́ mo jẹ́ ẹlẹ́ran ara, tí a ti tà sábẹ́ ẹ̀ṣẹ̀.+ 15 Ohun tí mò ń ṣe kò yé mi. Torí kì í ṣe ohun tí mo fẹ́ ni mò ń ṣe, àmọ́ ohun tí mo kórìíra ni mò ń ṣe. 16 Síbẹ̀, tí mo bá ń ṣe ohun tí mi ò fẹ́, á jẹ́ pé mo gbà pé Òfin dára nìyẹn. 17 Àmọ́ ní báyìí, ẹni tó ń ṣe é kì í ṣe èmi mọ́, ẹ̀ṣẹ̀ tó ń gbé inú mi ni.+ 18 Nítorí mo mọ̀ pé nínú mi, ìyẹn, nínú ẹran ara mi, kò sí ohun rere kankan níbẹ̀; torí ó ń wù mí láti ṣe ohun tó dára, àmọ́ mi ò ní agbára láti ṣe é.+ 19 Nítorí kì í ṣe rere tí mo fẹ́ ni mò ń ṣe, búburú tí mi ò fẹ́ ni mò ń ṣe. 20 Torí náà, tó bá jẹ́ pé ohun tí mi ò fẹ́ ni mò ń ṣe, ẹni tó ń ṣe é kì í ṣe èmi mọ́, ẹ̀ṣẹ̀ tó ń gbé inú mi ni.
21 Mo wá rí òfin yìí nínú ọ̀rọ̀ mi pé: Nígbà tí mo bá fẹ́ ṣe ohun tí ó tọ́, ohun tó burú ló máa ń wà lọ́kàn mi.+ 22 Nínú mi lọ́hùn-ún,+ mo nífẹ̀ẹ́ òfin Ọlọ́run gan-an, 23 àmọ́ mo rí òfin míì nínú ara* mi+ tó ń bá òfin tó ń darí èrò mi jagun, tó sì ń sọ mí di ẹrú òfin ẹ̀ṣẹ̀+ tó wà nínú ara* mi. 24 Èmi abòṣì èèyàn! Ta ló máa gbà mí lọ́wọ́ ara tó ń kú lọ yìí? 25 Ọpẹ́ ni fún Ọlọ́run nípasẹ̀ Jésù Kristi Olúwa wa! Torí náà, nínú èrò inú mi, mo jẹ́ ẹrú òfin Ọlọ́run, àmọ́ nínú ẹran ara mi, mo jẹ́ ẹrú òfin ẹ̀ṣẹ̀.+
8 Nítorí náà, kò sí ìdálẹ́bi kankan fún àwọn tó wà ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú Kristi Jésù. 2 Nítorí òfin ẹ̀mí tó ń fúnni ní ìyè nínú Kristi Jésù ti dá ọ sílẹ̀+ kúrò lọ́wọ́ òfin ẹ̀ṣẹ̀ àti ti ikú. 3 Ohun tí Òfin kò lè ṣe+ torí pé ẹran ara kò jẹ́ kó lágbára+ ni Ọlọ́run ṣe bó ṣe rán Ọmọ rẹ̀+ jáde bí èèyàn ẹlẹ́ṣẹ̀,+ kó lè mú ẹ̀ṣẹ̀ kúrò, ó sì ń tipa bẹ́ẹ̀ dá ẹran ara ẹ̀ṣẹ̀ lẹ́bi, 4 kí ohun òdodo tí Òfin béèrè lè ṣẹ nínú àwa+ tí à ń rìn nípa tẹ̀mí,+ kì í ṣe nípa tara. 5 Nítorí àwọn tó ń gbé ìgbé ayé tara máa ń ronú nípa àwọn nǹkan tara,+ àmọ́ àwọn tó ń gbé ìgbé ayé tẹ̀mí máa ń ronú nípa àwọn nǹkan tẹ̀mí.+ 6 Nítorí ríronú nípa àwọn nǹkan tara ń yọrí sí ikú,+ àmọ́ ríronú nípa àwọn nǹkan tẹ̀mí ń yọrí sí ìyè àti àlàáfíà;+ 7 torí pé ríronú nípa àwọn nǹkan tara ń sọni di ọ̀tá Ọlọ́run,+ nítorí kò sí lábẹ́ òfin Ọlọ́run, bẹ́ẹ̀ ni, kò lè sí níbẹ̀. 8 Torí náà, àwọn tó ń gbé ìgbé ayé tara kò lè ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run.
9 Tó bá jẹ́ pé òótọ́ ni ẹ̀mí Ọlọ́run ń gbé inú yín, á jẹ́ pé ìgbé ayé tẹ̀mí lẹ̀ ń gbé,+ kì í ṣe tara. Àmọ́ tí ẹnì kan ò bá ní ẹ̀mí Kristi, ẹni náà kì í ṣe tirẹ̀. 10 Ṣùgbọ́n tí Kristi bá wà ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú yín,+ ara yín jẹ́ òkú nítorí ẹ̀ṣẹ̀, ṣùgbọ́n ẹ̀mí ń mú ìyè wá nítorí òdodo. 11 Ní báyìí, tí ẹ̀mí ẹni tó gbé Jésù dìde kúrò nínú ikú bá ń gbé inú yín, ẹni tó gbé Kristi Jésù dìde kúrò nínú ikú+ pẹ̀lú yóò fi ẹ̀mí rẹ̀ tó ń gbé inú yín sọ ara kíkú yín di ààyè.+
12 Nítorí náà, ẹ̀yin ará, a wà lábẹ́ ọ̀ranyàn, àmọ́ kì í ṣe láti máa gbé ìgbé ayé tara, ká lè máa ṣe ìfẹ́ tara;+ 13 torí ó dájú pé ẹ máa kú, tí ẹ bá ń gbé ìgbé ayé tara; àmọ́ tí ẹ bá fi ẹ̀mí lu àwọn iṣẹ́ tara pa,+ ẹ ó yè.+ 14 Nítorí gbogbo àwọn tí ẹ̀mí Ọlọ́run ń darí ni ọmọ Ọlọ́run lóòótọ́.+ 15 Torí kì í ṣe ẹ̀mí ìsìnrú tó ń múni pa dà sínú ìbẹ̀rù lẹ gbà, ẹ̀mí ìsọdọmọ lẹ gbà, ẹ̀mí tó ń mú ká ké jáde pé: “Ábà,* Bàbá!”+ 16 Ẹ̀mí fúnra rẹ̀ ń jẹ́rìí pẹ̀lú ẹ̀mí wa + pé ọmọ Ọlọ́run ni wá.+ 17 Nígbà náà, tí a bá jẹ́ ọmọ, ajogún ni wá pẹ̀lú, lóòótọ́ a jẹ́ ajogún Ọlọ́run, àmọ́ a jẹ́ ajùmọ̀jogún+ pẹ̀lú Kristi, kìkì tí a bá jọ jìyà,+ kí a lè ṣe wá lógo pẹ̀lú rẹ̀.+
18 Nítorí mo gbà pé àwọn ìyà àsìkò yìí kò já mọ́ nǹkan kan tí a bá fi wé ògo tí a máa fi hàn nínú wa.+ 19 Torí ìṣẹ̀dá ń dúró de ìfihàn àwọn ọmọ Ọlọ́run+ lójú méjèèjì. 20 Nítorí a tẹ ìṣẹ̀dá lórí ba fún asán,+ kì í ṣe nípa ìfẹ́ òun fúnra rẹ̀, àmọ́ nípasẹ̀ ẹni tó tẹ̀ ẹ́ lórí ba, nítorí ìrètí, 21 kí a lè dá ìṣẹ̀dá fúnra rẹ̀ sílẹ̀+ lọ́wọ́ ẹrú ìdíbàjẹ́, kí ó sì lè ní òmìnira ológo ti àwọn ọmọ Ọlọ́run. 22 Nítorí a mọ̀ pé gbogbo ìṣẹ̀dá jọ ń kérora nìṣó, wọ́n sì jọ wà nínú ìrora títí di báyìí. 23 Kì í ṣe ìyẹn nìkan, àmọ́ àwa fúnra wa pẹ̀lú tí a ní àkọ́so, ìyẹn, ẹ̀mí náà, bẹ́ẹ̀ ni, àwa fúnra wa ń kérora nínú ara wa,+ bí a ṣe ń dúró de ìsọdọmọ+ lójú méjèèjì, ìyẹn ìtúsílẹ̀ kúrò nínú ara wa nípasẹ̀ ìràpadà. 24 Nítorí a gbà wá là nínú ìrètí yìí; àmọ́ ìrètí tí èèyàn bá ti rí kì í ṣe ìrètí mọ́, torí tí èèyàn bá ti rí nǹkan, ṣé á tún máa retí rẹ̀ ni? 25 Ṣùgbọ́n tí a bá ń retí+ ohun tí a kò rí,+ a ó máa fi ìfaradà dúró dè é+ lójú méjèèjì.
26 Lọ́nà kan náà, ẹ̀mí tún ń ràn wá lọ́wọ́ nínú àìlera wa;+ torí ìṣòro ibẹ̀ ni pé a ò mọ ohun tó yẹ ká fi sínú àdúrà bó ṣe yẹ ká ṣe, àmọ́ ẹ̀mí fúnra rẹ̀ ń bá wa bẹ̀bẹ̀ nígbà tí a wà nínú ìrora inú lọ́hùn-ún.* 27 Ẹni tó ń wá inú ọkàn+ mọ ohun tí ẹ̀mí ń sọ, nítorí ó ń bá àwọn ẹni mímọ́ bẹ̀bẹ̀ bí Ọlọ́run ṣe fẹ́.
28 A mọ̀ pé Ọlọ́run ń mú kí gbogbo ohun tó ń ṣe máa ṣiṣẹ́ pọ̀ fún ire àwọn tó nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run, àwọn tí a pè nítorí ìfẹ́ rẹ̀;+ 29 nítorí àwọn tó kọ́kọ́ fún ní àfiyèsí ló tún yàn ṣáájú láti jẹ́ àwòrán Ọmọ rẹ̀,+ kó lè jẹ́ àkọ́bí+ láàárín ọ̀pọ̀ arákùnrin.+ 30 Yàtọ̀ síyẹn, àwọn tó yàn ṣáájú+ ni àwọn tó pè;+ àwọn tó pè ni àwọn tó kéde ní olódodo.+ Níkẹyìn, àwọn tó kéde ní olódodo ni àwọn tó ṣe lógo.+
31 Kí ni ká wá sọ sọ́rọ̀ yìí? Tí Ọlọ́run bá wà lẹ́yìn wa, ta ló lè dènà wa?+ 32 Bí kò ṣe dá Ọmọ rẹ̀ pàápàá sí, àmọ́ tó fi í lélẹ̀ nítorí gbogbo wa,+ ṣé kò wá ní fi gbogbo ohun mìíràn kún Ọmọ rẹ̀ fún wa nítorí inú rere rẹ̀ ni? 33 Ta ló máa fẹ̀sùn kan àwọn àyànfẹ́ Ọlọ́run? + Ọlọ́run ni Ẹni tó pè wọ́n ní olódodo.+ 34 Ta ló máa dá wọn lẹ́bi? Kristi Jésù ló kú, bẹ́ẹ̀ ni, yàtọ̀ síyẹn, òun la gbé dìde, tó wà ní ọwọ́ ọ̀tún Ọlọ́run,+ tó sì ń bá wa bẹ̀bẹ̀.+
35 Ta ló máa yà wá kúrò nínú ìfẹ́ Kristi? + Ṣé ìpọ́njú ni àbí wàhálà àbí inúnibíni àbí ebi àbí ìhòòhò àbí ewu àbí idà?+ 36 Bó ṣe wà lákọsílẹ̀ pé: “Torí rẹ ni wọ́n ṣe ń pa wá láti àárọ̀ ṣúlẹ̀; wọ́n ti kà wá sí àgùntàn tó wà fún pípa.”+ 37 Kàkà bẹ́ẹ̀, nínú gbogbo àwọn nǹkan yìí, à ń ja àjàṣẹ́gun+ nípasẹ̀ ẹni tó nífẹ̀ẹ́ wa. 38 Torí ó dá mi lójú pé kì í ṣe ikú tàbí ìyè tàbí àwọn áńgẹ́lì tàbí àwọn ìjọba tàbí àwọn ohun tó wà nísinsìnyí tàbí àwọn ohun tó ń bọ̀ tàbí àwọn agbára+ 39 tàbí ibi gíga tàbí ibi jíjìn tàbí ìṣẹ̀dá èyíkéyìí mìíràn ló máa lè yà wá kúrò nínú ìfẹ́ Ọlọ́run tó wà nínú Kristi Jésù Olúwa wa.
9 Mò ń sọ òtítọ́ nínú Kristi; mi ò parọ́, bí ẹ̀rí ọkàn mi ṣe ń jẹ́rìí pẹ̀lú mi nínú ẹ̀mí mímọ́, 2 pé mo ní ẹ̀dùn ọkàn tó pọ̀ àti ìrora tí kò dáwọ́ dúró nínú ọkàn mi. 3 Nítorí ì bá wù mí kí a yà mí sọ́tọ̀ bí ẹni ègún kúrò lọ́dọ̀ Kristi nítorí àwọn arákùnrin mi, àwọn ìbátan mi nípa tara, 4 àwọn ọmọ Ísírẹ́lì. Àwọn ni ìsọdọmọ + jẹ́ tiwọn àti ògo àti àwọn májẹ̀mú+ àti gbígba Òfin+ àti iṣẹ́ ìsìn mímọ́+ àti àwọn ìlérí.+ 5 Àwọn ni ọmọ àwọn baba ńlá+ tí Kristi jáde wá látọ̀dọ̀ wọn nípa tara.+ Ìyìn ni fún Ọlọ́run, olórí ohun gbogbo, títí láé. Àmín.
6 Àmọ́, kì í ṣe pé ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ti kùnà. Torí kì í ṣe gbogbo àwọn tó wá látinú Ísírẹ́lì ni “Ísírẹ́lì” lóòótọ́.+ 7 Bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe torí pé wọ́n jẹ́ ọmọ* Ábúráhámù+ ni gbogbo wọn fi jẹ́ ọmọ; kàkà bẹ́ẹ̀, “Látọ̀dọ̀ Ísákì ni ọmọ* rẹ yóò ti wá.”+ 8 Ìyẹn ni pé, àwọn ọmọ nípa tara kì í ṣe àwọn ọmọ Ọlọ́run lóòótọ́,+ àmọ́ àwọn ọmọ tó wá nípasẹ̀ ìlérí+ ni a kà sí ọmọ.* 9 Nítorí ìlérí náà lọ báyìí pé: “Ní àkókò yìí, màá wá, Sérà yóò sì bí ọmọkùnrin kan.”+ 10 Kì í ṣe ìgbà yẹn nìkan, àmọ́ ó tún ṣẹlẹ̀ nígbà tí Rèbékà lóyún ìbejì fún ọkùnrin kan, ìyẹn Ísákì baba ńlá wa;+ 11 torí nígbà tí wọn ò tíì bí wọn tàbí tí wọn ò tíì ṣe rere tàbí búburú, kí ìpinnu Ọlọ́run lórí yíyàn má bàa jẹ́ nípa àwọn iṣẹ́, àmọ́ kó jẹ́ nípa Ẹni tó ń peni, 12 a sọ fún un pé: “Ẹ̀gbọ́n ni yóò jẹ́ ẹrú àbúrò.”+ 13 Bó ṣe wà lákọsílẹ̀ pé: “Mo nífẹ̀ẹ́ Jékọ́bù, àmọ́ mo kórìíra Ísọ̀.”+
14 Kí wá ni ká sọ? Ṣé Ọlọ́run jẹ́ aláìṣòdodo ni? Kò rí bẹ́ẹ̀ rárá! + 15 Torí ó sọ fún Mósè pé: “Èmi yóò ṣàánú ẹni tí èmi yóò ṣàánú, èmi yóò sì yọ́nú sí ẹni tí èmi yóò yọ́nú sí.”+ 16 Nítorí náà, kò sí lọ́wọ́ ẹni tó ń fẹ́ tàbí lọ́wọ́ ìsapá* ẹni náà, àmọ́ ọwọ́ Ọlọ́run tó ń ṣàánú ló wà.+ 17 Nítorí Ìwé Mímọ́ sọ fún Fáráò pé: “Ìdí tí mo fi jẹ́ kí o máa wà nìṣó ni pé: kí n lè fi agbára mi hàn nípasẹ̀ rẹ àti pé kí a lè ròyìn orúkọ mi ní gbogbo ayé.”+ 18 Torí náà, ẹni tó bá wù ú ló ń ṣàánú, ẹni tó bá sì wù ú ló ń jẹ́ kó di olóríkunkun.+
19 Nítorí náà, wàá sọ fún mi pé: “Kí ló dé tó ṣì fi ń rí àléébù? Àbí ta ló lè dènà rẹ̀ pé kó má ṣe ohun tó bá fẹ́?” 20 Ta ni ọ́, ìwọ èèyàn, tí o fi ń gbó Ọlọ́run lẹ́nu?+ Ṣé ohun tí wọ́n mọ máa ń sọ fún ẹni tó mọ ọ́n pé: “Kí ló dé tí o fi mọ mí báyìí?”+ 21 Kí wá ni? Ṣé amọ̀kòkò ò láṣẹ lórí amọ̀+ láti fi lára ìṣùpọ̀ rẹ̀ mọ ohun èlò* kan fún ìlò tó lọ́lá, kí ó sì fi lára rẹ̀ mọ ohun èlò míì fún ìlò tí kò lọ́lá? 22 Nígbà náà, bí Ọlọ́run tó jẹ́ ìfẹ́ rẹ̀ pé kó fi ìrunú rẹ̀ hàn, kó sì jẹ́ ká mọ agbára òun, bá fi ọ̀pọ̀ sùúrù gba àwọn ohun èlò ìrunú tó yẹ fún ìparun láyè, 23 tó sì ṣe èyí láti jẹ́ ká mọ ọrọ̀ ògo rẹ̀ lórí àwọn ohun èlò àánú,+ èyí tó ti pèsè sílẹ̀ fún ògo, 24 ìyẹn àwa tí ó pè, kì í ṣe láti àárín àwọn Júù nìkan, àmọ́ láti àárín àwọn orílẹ̀-èdè+ pẹ̀lú, kí wá ni ká sọ? 25 Ó rí bí ó ṣe sọ nínú ìwé Hósíà pé: “Màá pe àwọn tí kì í ṣe èèyàn mi+ ní ‘àwọn èèyàn mi,’ màá sì pe ẹni tí kì í ṣe olùfẹ́ ní ‘àyànfẹ́’;+ 26 bákan náà, níbi tí a ti sọ fún wọn pé, ‘Ẹ kì í ṣe èèyàn mi,’ ibẹ̀ la ó ti pè wọ́n ní ‘àwọn ọmọ Ọlọ́run alààyè.’”+
27 Yàtọ̀ síyẹn, Àìsáyà kéde nípa Ísírẹ́lì pé: “Bí iye àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tiẹ̀ pọ̀ bí iyanrìn òkun, àṣẹ́kù wọn nìkan ni a ó gbà là.+ 28 Nítorí Jèhófà* máa ní kí gbogbo ayé jíhìn, á parí rẹ̀, kò sì ní fi falẹ̀.”*+ 29 Bákan náà, bí Àìsáyà ṣe sọ tẹ́lẹ̀ pé: “Tí kì í bá ṣe pé Jèhófà* Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun ṣẹ́ ọmọ* kan kù sílẹ̀ fún wa, à bá ti dà bíi Sódómù gẹ́lẹ́, à bá sì ti jọ Gòmórà.”+
30 Kí wá ni ká sọ? Pé bí àwọn èèyàn orílẹ̀-èdè ò tiẹ̀ lépa òdodo, ọwọ́ wọn tẹ òdodo,+ òdodo tó wá látinú ìgbàgbọ́;+ 31 àmọ́ bí Ísírẹ́lì tiẹ̀ ń lépa òfin òdodo, ọwọ́ rẹ̀ kò tẹ òfin náà. 32 Kí nìdí? Torí pé wọ́n lépa rẹ̀ nípa àwọn iṣẹ́, kì í ṣe nípa ìgbàgbọ́. Wọ́n kọsẹ̀ lára “òkúta ìkọ̀sẹ̀”+ náà; 33 bó ṣe wà lákọsílẹ̀ pé: “Wò ó! Màá fi òkúta+ ìkọ̀sẹ̀ kan àti àpáta agbéniṣubú lélẹ̀ ní Síónì, àmọ́ ẹni tó bá gbé ìgbàgbọ́ rẹ̀ lé e kò ní rí ìjákulẹ̀.”+
10 Ẹ̀yin ará, ohun rere tó wà lọ́kàn mi àti ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀ mi sí Ọlọ́run nítorí wọn ni pé kí wọ́n rí ìgbàlà.+ 2 Nítorí mo jẹ́rìí wọn pé wọ́n ní ìtara fún Ọlọ́run,+ àmọ́ kì í ṣe pẹ̀lú ìmọ̀ tó péye. 3 Bí wọn ò ṣe mọ òdodo Ọlọ́run,+ àmọ́ tó jẹ́ pé bí wọ́n á ṣe gbé tiwọn kalẹ̀ ni wọ́n ń wá,+ wọn ò fi ara wọn sábẹ́ òdodo Ọlọ́run.+ 4 Nítorí Kristi ni òpin Òfin,+ kí gbogbo ẹni tó ní ìgbàgbọ́ lè ní òdodo.+
5 Nítorí Mósè kọ̀wé nípa òdodo tó wá látinú Òfin pé: “Yóò mú kí ẹni tó bá ń pa àwọn ohun tó sọ mọ́ wà láàyè.”+ 6 Àmọ́ òdodo tó wá látinú ìgbàgbọ́ sọ pé: “Má sọ lọ́kàn rẹ pé,+ ‘Ta ló máa lọ sí ọ̀run?’+ ìyẹn, láti mú Kristi wá 7 tàbí, ‘Ta ló máa lọ sínú ọ̀gbun àìnísàlẹ̀?’+ ìyẹn, láti mú Kristi gòkè kúrò nínú ikú.” 8 Àmọ́ kí ni Ìwé Mímọ́ sọ? “Tòsí rẹ ni ọ̀rọ̀ náà wà, ní ẹnu rẹ àti ọkàn rẹ”;+ ìyẹn, “ọ̀rọ̀” ìgbàgbọ́, tí à ń wàásù. 9 Nítorí tí o bá ń fi ẹnu rẹ kéde ní gbangba pé Jésù ni Olúwa,+ tí o sì ní ìgbàgbọ́ nínú ọkàn rẹ pé Ọlọ́run gbé e dìde kúrò nínú ikú, a ó gbà ọ́ là. 10 Nítorí ọkàn la fi ń ní ìgbàgbọ́ kí a lè jẹ́ olódodo, àmọ́ ẹnu la fi ń kéde ní gbangba+ kí a lè rí ìgbàlà.
11 Ìwé Mímọ́ sọ pé: “Kò sí ẹni tó bá gbé ìgbàgbọ́ rẹ̀ lé e tó máa rí ìjákulẹ̀.”+ 12 Nítorí kò sí ìyàtọ̀ nínú Júù àti Gíríìkì.+ Torí Olúwa kan náà ló wà lórí gbogbo wọn, ẹni tó lawọ́* sí gbogbo àwọn tó ń ké pè é. 13 Nítorí “gbogbo ẹni tó bá ń ké pe orúkọ Jèhófà* yóò rí ìgbàlà.”+ 14 Àmọ́, báwo ni wọ́n á ṣe ké pè é tí wọn ò bá ní ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀? Báwo sì ni wọ́n á ṣe ní ìgbàgbọ́ nínú ẹni tí wọn ò gbọ́ nípa rẹ̀? Báwo ni wọ́n á ṣe gbọ́ tí kò bá sí ẹni tó máa wàásù? 15 Báwo ni wọ́n á sì ṣe wàásù láìjẹ́ pé a rán wọn jáde?+ Gẹ́gẹ́ bó ṣe wà lákọsílẹ̀ pé: “Ẹsẹ̀ àwọn tó ń kéde ìhìn rere àwọn ohun rere mà rẹwà o!”+
16 Síbẹ̀, kì í ṣe gbogbo wọn ló ṣègbọràn sí ìhìn rere náà. Nítorí Àìsáyà sọ pé: “Jèhófà,* ta ló ti nígbàgbọ́ nínú ohun tó gbọ́ lọ́dọ̀ wa?”*+ 17 Torí náà, ìgbàgbọ́ ń tẹ̀ lé ohun tí a gbọ́.+ Ohun tí a gbọ́ sì jẹ́ nípasẹ̀ ọ̀rọ̀ Kristi. 18 Àmọ́ mo béèrè pé, Ṣé wọn ò gbọ́ ni? Wọ́n kúkú gbọ́. Torí, ní tòótọ́, “ohùn wọn ti dún jáde lọ sí gbogbo ayé, iṣẹ́ tí wọ́n ń jẹ́ sì ti dé ìkángun ilẹ̀ ayé tí à ń gbé.”+ 19 Àmọ́ mo béèrè pé, Ṣé Ísírẹ́lì ò mọ̀ ni?+ Wọ́n kúkú mọ̀. Lákọ̀ọ́kọ́, Mósè sọ pé: “Màá fi àwọn tí kì í ṣe orílẹ̀-èdè mú kí ẹ jowú; màá fi orílẹ̀-èdè òmùgọ̀ mú kí ẹ gbaná jẹ.”+ 20 Àmọ́ Àìsáyà fi ìgboyà sọ̀rọ̀, ó ní: “Àwọn tí kò wá mi ti rí mi,+ àwọn tí kò béèrè mi ti wá mọ̀ mí.”+ 21 Àmọ́, ó sọ nípa Ísírẹ́lì pé: “Láti àárọ̀ ṣúlẹ̀, mo tẹ́ ọwọ́ mi sí àwọn èèyàn tó jẹ́ aláìgbọràn àti olóríkunkun.”+
11 Nígbà náà, mo béèrè pé, Ṣé Ọlọ́run ti kọ àwọn èèyàn rẹ̀ sílẹ̀ ni?+ Rárá o! Nítorí ọmọ Ísírẹ́lì ni èmi náà, àtọmọdọ́mọ* Ábúráhámù, láti ẹ̀yà Bẹ́ńjámínì. 2 Ọlọ́run ò kọ àwọn èèyàn rẹ̀ sílẹ̀, àwọn tó kọ́kọ́ mọ̀.+ Ṣé ẹ ò mọ ohun tí ìwé mímọ́ sọ nípa Èlíjà ni, bí ó ṣe ń fi ẹjọ́ Ísírẹ́lì sùn nígbà tó ń bẹ Ọlọ́run? 3 “Jèhófà,* wọ́n ti pa àwọn wòlíì rẹ, wọ́n ti hú àwọn pẹpẹ rẹ kúrò, èmi nìkan ló ṣẹ́ kù, wọ́n sì fẹ́ gba ẹ̀mí* mi.”+ 4 Síbẹ̀, èsì wo ni ó gbọ́ láti ọ̀run? “Mo ti ṣẹ́ ẹgbẹ̀rún méje (7,000) ọkùnrin kù fún ara mi, àwọn ọkùnrin tí kò kúnlẹ̀ fún Báálì.”+ 5 Lọ́nà kan náà, ní àkókò yìí, àṣẹ́kù kan wà+ tí a yàn nípasẹ̀ inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí. 6 Ní báyìí, tó bá jẹ́ nípasẹ̀ inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí ni,+ á jẹ́ pé kì í ṣe nípasẹ̀ àwọn iṣẹ́ mọ́;+ àìjẹ́ bẹ́ẹ̀, inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí náà kò ní jẹ́ inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí mọ́.
7 Kí wá ni? Ísírẹ́lì kò rí ohun tó ń wá lójú méjèèjì gbà, àmọ́ àwọn tí a yàn rí i gbà.+ Ọkàn àwọn yòókù ti yigbì,+ 8 bó ṣe wà lákọsílẹ̀ pé: “Ọlọ́run ti fún wọn ní ẹ̀mí oorun àsùnwọra,+ ojú tí kò ríran àti etí tí kò gbọ́ràn, títí di òní olónìí.”+ 9 Bákan náà, Dáfídì sọ pé: “Jẹ́ kí tábìlì wọn di ìdẹkùn àti pańpẹ́ àti ohun ìkọ̀sẹ̀ àti ẹ̀san fún wọn. 10 Jẹ́ kí ojú wọn ṣú, kí wọ́n má lè ríran, sì mú kí ẹ̀yìn wọn tẹ̀ ba nígbà gbogbo.”+
11 Nítorí náà, mo béèrè pé, Ṣé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kọsẹ̀ tí wọ́n fi ṣubú pátápátá ni? Rárá o! Àmọ́ bí wọ́n ṣe ṣi ẹsẹ̀ gbé ló mú ìgbàlà wá fún àwọn èèyàn orílẹ̀-èdè, èyí sì mú kí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì máa jowú.+ 12 Ní báyìí, tí bí wọ́n ṣe ṣi ẹsẹ̀ gbé bá yọrí sí ọrọ̀ fún ayé, tí bí wọ́n ṣe dín kù sì yọrí sí ọrọ̀ fún àwọn èèyàn orílẹ̀-èdè,+ ẹ wo bí ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ iye wọn yóò ṣe yọrí sí ohun tó jù bẹ́ẹ̀ lọ!
13 Ní báyìí, ẹ̀yin tí ẹ wá láti àwọn orílẹ̀-èdè ni mo fẹ́ bá sọ̀rọ̀. Bí mo ṣe jẹ́ àpọ́sítélì fún àwọn orílẹ̀-èdè,+ mo ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ mi lógo*+ 14 bóyá màá lè rọ́nà mú kí àwọn èèyàn* mi jowú, kí n sì gba díẹ̀ lára wọn là. 15 Nítorí bí títa wọ́n nù+ bá yọrí sí ìpadàrẹ́ fún ayé, ṣé gbígbà wọ́n kò ní yọrí sí ìyè kúrò nínú ikú ni? 16 Síwájú sí i, tí apá tí a mú gẹ́gẹ́ bí àkọ́so lára ìṣùpọ̀ bá jẹ́ mímọ́, gbogbo rẹ̀ yóò jẹ́ mímọ́ pẹ̀lú; tí gbòǹgbò bá sì jẹ́ mímọ́, àwọn ẹ̀ka yóò jẹ́ bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú.
17 Àmọ́, tí a bá ṣẹ́ àwọn ẹ̀ka kan kúrò, tí a lọ́ ìwọ tí o jẹ́ ólífì inú igbó mọ́ àárín wọn, tí o sì wá pín nínú èròjà ilẹ̀ tó wà fún gbòǹgbò igi ólífì náà, 18 má ṣe máa gbéra ga* sí àwọn ẹ̀ka náà. Torí tí o bá gbéra ga* sí wọn,+ rántí pé ìwọ kọ́ lo gbé gbòǹgbò dúró, gbòǹgbò ló gbé ọ dúró. 19 Nígbà náà, wàá sọ pé: “Ńṣe ni wọ́n ṣẹ́ àwọn ẹ̀ka kan kúrò, kí wọ́n lè lọ́ mi wọlé.”+ 20 Òótọ́ nìyẹn! Nítorí àìnígbàgbọ́ wọn, a ṣẹ́ wọn kúrò,+ àmọ́ ìgbàgbọ́ mú kí ìwọ dúró.+ Má ṣe gbéra ga, àmọ́ ṣe ni kí o bẹ̀rù. 21 Nítorí bí Ọlọ́run kò bá dá àwọn ẹ̀ka igi gangan sí, kò ní dá ìwọ náà sí. 22 Nítorí náà, ronú nípa inú rere Ọlọ́run+ àti bó ṣe ń fìyà jẹni. Ìyà wà fún àwọn tó ṣubú,+ àmọ́ inú rere Ọlọ́run wà fún ìwọ, kìkì bí o bá dúró nínú inú rere rẹ̀; àìjẹ́ bẹ́ẹ̀, a ó ṣẹ́ ìwọ náà kúrò. 23 Tí àwọn náà bá kúrò nínú àìnígbàgbọ́ wọn, a ó lọ́ wọn wọlé,+ nítorí Ọlọ́run lè lọ́ wọn wọlé pa dà. 24 Nítorí tó bá jẹ́ pé a gé ọ kúrò lára igi ólífì inú igbó, tí a sì lọ́ ọ wọlé sínú igi ólífì inú ọgbà, ẹ wo bó ṣe máa rọrùn tó láti lọ́ àwọn tó jẹ́ ẹ̀ka igi ólífì gangan wọlé pa dà sínú igi ólífì tiwọn!
25 Nítorí mi ò fẹ́ kí ẹ ṣaláìmọ àṣírí mímọ́ yìí,+ ẹ̀yin ará, kí ẹ má bàa gbọ́n lójú ara yín: Pé ọkàn àwọn èèyàn Ísírẹ́lì yigbì lápá kan títí iye àwọn èèyàn àwọn orílẹ̀-èdè tó máa wọlé á fi pé, 26 báyìí la ṣe máa gba gbogbo Ísírẹ́lì+ là. Gẹ́gẹ́ bó ṣe wà lákọsílẹ̀ pé: “Olùdáǹdè* máa wá láti Síónì,+ á sì yí àwọn ìwà tí kò bá ìfẹ́ Ọlọ́run mu pa dà kúrò lọ́dọ̀ Jékọ́bù. 27 Èyí sì ni májẹ̀mú tí mo bá wọn dá,+ nígbà tí mo bá mú àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wọn kúrò.”+ 28 Lóòótọ́, tó bá dọ̀rọ̀ ìhìn rere, ọ̀tá ni wọ́n jẹ́ nítorí yín, àmọ́ tó bá dọ̀rọ̀ àwọn tí Ọlọ́run yàn, ẹni ọ̀wọ́n ni wọ́n jẹ́ nítorí àwọn baba ńlá wọn.+ 29 Nítorí Ọlọ́run kò ní kábàámọ̀ àwọn ẹ̀bùn tó fún wọn àti pípè tó pè wọ́n. 30 Nítorí bí ẹ ṣe fìgbà kan jẹ́ aláìgbọràn sí Ọlọ́run,+ àmọ́ tí a fi àánú hàn sí+ yín ní báyìí nítorí àìgbọràn wọn,+ 31 bẹ́ẹ̀ náà ni bí wọ́n ṣe jẹ́ aláìgbọràn ní báyìí ṣe yọrí sí àánú fún yín, kí a lè fi àánú hàn sí àwọn náà ní báyìí. 32 Nítorí Ọlọ́run ti sé gbogbo wọn pọ̀ mọ́ inú àìgbọràn,+ kí ó lè fi àánú hàn sí gbogbo wọn.+
33 Ọrọ̀ àti ọgbọ́n àti ìmọ̀ Ọlọ́run mà jinlẹ̀ o! Ẹ wo bí àwọn ìdájọ́ rẹ̀ ṣe jẹ́ àwámáridìí tó, tí àwọn ọ̀nà rẹ̀ sì kọjá àwárí! 34 Nítorí “ta ló mọ èrò Jèhófà,* ta sì ni agbani-nímọ̀ràn rẹ̀?”+ 35 Àbí, “ta ló ti kọ́kọ́ fún un ní nǹkan, tó fi gbọ́dọ̀ san án pa dà fún un?”+ 36 Torí pé ọ̀dọ̀ rẹ̀ ni ohun gbogbo ti wá, ipasẹ̀ rẹ̀ ni wọ́n fi wà, tìtorí rẹ̀ ni wọ́n sì ṣe wà. Òun ni kí ògo jẹ́ tirẹ̀ títí láé. Àmín.
12 Nítorí náà, mo fi ìyọ́nú Ọlọ́run bẹ̀ yín, ẹ̀yin ará, pé kí ẹ fi ara yín+ fún Ọlọ́run ní ẹbọ ààyè, tó jẹ́ mímọ́,+ tó sì ṣe ìtẹ́wọ́gbà, kí ẹ lè ṣe iṣẹ́ ìsìn mímọ́ pẹ̀lú agbára ìrònú yín.+ 2 Ẹ má sì jẹ́ kí ètò àwọn nǹkan yìí* máa darí yín, àmọ́ ẹ para dà nípa yíyí èrò inú yín pa dà,+ kí ẹ lè fúnra yín ṣàwárí+ ìfẹ́ Ọlọ́run tí ó dára, tí ó ṣe ìtẹ́wọ́gbà, tí ó sì pé.
3 Torí nípasẹ̀ inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí tí a fún mi, mo sọ fún gbogbo ẹni tó wà láàárín yín níbẹ̀ pé kó má ro ara rẹ̀ ju bó ṣe yẹ lọ,+ àmọ́ kó máa ronú lọ́nà tó fi hàn pé ó láròjinlẹ̀, bí Ọlọ́run ṣe fún kálukú ní ìwọ̀n ìgbàgbọ́.*+ 4 Nítorí bí ọ̀pọ̀ ẹ̀yà ara ṣe wà nínú ara kan,+ àmọ́ tí gbogbo ẹ̀yà ara kì í ṣe iṣẹ́ kan náà, 5 bẹ́ẹ̀ ni àwa, bí a tiẹ̀ pọ̀, a jẹ́ ara kan ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú Kristi, àmọ́ lẹ́nì kọ̀ọ̀kan, a jẹ́ ẹ̀yà ara fún ẹnì kejì wa.+ 6 Nígbà tí a sì ti ní àwọn ẹ̀bùn tó yàtọ̀ síra nípasẹ̀ inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí tí a fún wa,+ tó bá jẹ́ ti àsọtẹ́lẹ̀ ni, ẹ jẹ́ ká máa sọ tẹ́lẹ̀ bí ìgbàgbọ́ wa ṣe tó; 7 tó bá jẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ ni, ẹ jẹ́ kí a wà lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ yìí; tàbí ẹni tó ń kọ́ni, kó wà lẹ́nu kíkọ́ni rẹ̀;+ 8 tàbí ẹni tó ń fúnni níṣìírí,* kó máa fúnni níṣìírí;*+ ẹni tó ń pín nǹkan fúnni,* kó máa ṣe é tinútinú;+ ẹni tó ń ṣe àbójútó,* kó máa ṣe é kárakára;*+ ẹni tó ń ṣàánú, kó máa fi ọ̀yàyà ṣe é.+
9 Ẹ jẹ́ kí ìfẹ́ yín wà láìsí ẹ̀tàn.*+ Ẹ kórìíra ohun búburú;+ ẹ rọ̀ mọ́ ohun rere. 10 Nínú ìfẹ́ ará, ẹ ní ìfẹ́ oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ fún ara yín. Nínú bíbu ọlá fún ara yín, ẹ mú ipò iwájú.*+ 11 Ẹ máa ṣiṣẹ́ kára,* ẹ má ṣọ̀lẹ.*+ Kí iná ẹ̀mí máa jó nínú yín.+ Ẹ máa ṣẹrú fún Jèhófà.*+ 12 Ẹ jẹ́ kí ìrètí tí ẹ ní máa fún yín láyọ̀. Ẹ máa fara da ìpọ́njú.+ Ẹ máa tẹra mọ́ àdúrà gbígbà.+ 13 Ẹ máa ṣàjọpín nǹkan pẹ̀lú àwọn ẹni mímọ́ kí wọ́n lè rí ohun tí wọ́n nílò.+ Ẹ máa ṣe aájò àlejò.+ 14 Ẹ máa súre fún àwọn tó ń ṣe inúnibíni;+ ẹ máa súre, ẹ má sì máa ṣépè.+ 15 Ẹ máa yọ̀ pẹ̀lú àwọn tó ń yọ̀; ẹ máa sunkún pẹ̀lú àwọn tó ń sunkún. 16 Bí ẹ ṣe ń ṣe sí ara yín ni kí ẹ máa ṣe sí àwọn ẹlòmíì; ẹ má ṣe máa ronú nípa àwọn ohun ńláńlá,* àmọ́ ẹ máa ronú nípa àwọn ohun tó rẹlẹ̀.+ Ẹ má ṣe jẹ́ ọlọ́gbọ́n lójú ara yín.+
17 Ẹ má ṣe fi ibi san ibi fún ẹnikẹ́ni.+ Ẹ jẹ́ kí ìrònú yín dá lé ohun tó dára lójú gbogbo èèyàn. 18 Tó bá ṣeé ṣe, nígbà tó bá ti jẹ́ pé ọwọ́ yín ló wà, ẹ wà ní àlàáfíà pẹ̀lú gbogbo èèyàn.+ 19 Ẹ má ṣe fúnra yín gbẹ̀san, ẹ̀yin olùfẹ́, àmọ́ ẹ fàyè sílẹ̀ fún ìrunú;*+ nítorí ó ti wà lákọsílẹ̀ pé: “Tèmi ni ẹ̀san; màá gbẹ̀san, ni Jèhófà* wí.”+ 20 Àmọ́ “tí ebi bá ń pa ọ̀tá rẹ, fún un ní oúnjẹ jẹ; tí òùngbẹ bá sì ń gbẹ ẹ́, fún un ní nǹkan mu; torí bí o ṣe ń ṣe èyí, wàá máa kó ẹyin iná jọ lé e lórí.”*+ 21 Má ṣe jẹ́ kí ibi ṣẹ́gun rẹ, àmọ́ máa fi ire ṣẹ́gun ibi.+
13 Kí gbogbo èèyàn* máa tẹrí ba fún àwọn aláṣẹ onípò gíga,+ nítorí kò sí àṣẹ kankan àfi èyí tó wá látọ̀dọ̀ Ọlọ́run;+ àwọn aláṣẹ tó wà ni a gbé sí àwọn ipò wọn tó ní ààlà látọ̀dọ̀ Ọlọ́run.+ 2 Nítorí náà, ẹni tó bá ta ko aláṣẹ ta ko ètò tí Ọlọ́run ṣe; àwọn tó bá ta kò ó máa gba ìdájọ́ sórí ara wọn. 3 Torí àwọn tó ń ṣàkóso jẹ́ ohun ẹ̀rù, kì í ṣe sí àwọn tó ń ṣe rere, àmọ́ sí àwọn tó ń ṣe búburú.+ Ṣé o kò fẹ́ kí ẹ̀rù aláṣẹ máa bà ọ́? Máa ṣe rere,+ wàá sì gba ìyìn nítorí rẹ̀; 4 torí òjíṣẹ́ Ọlọ́run ló jẹ́ sí ọ fún ire rẹ. Àmọ́ tí o bá ń ṣe ohun búburú, máa bẹ̀rù, nítorí kì í ṣàdédé gbé idà. Òjíṣẹ́ Ọlọ́run ni, ó ń gbẹ̀san láti fi ìrunú hàn sí* ẹni tó ń ṣe ohun búburú.
5 Torí náà, ìdí pàtàkì wà tó fi yẹ kí ẹ máa tẹrí ba, kì í ṣe nítorí ìrunú yẹn nìkan, àmọ́ ó jẹ́ nítorí ẹ̀rí ọkàn+ yín pẹ̀lú. 6 Ìdí nìyẹn tí ẹ tún fi ń san owó orí; nítorí wọ́n jẹ́ ìránṣẹ́ Ọlọ́run fún gbogbo èèyàn, wọ́n sì ń ṣe iṣẹ́ yìí nígbà gbogbo. 7 Ẹ fún gbogbo èèyàn ní ohun tí ó tọ́ sí wọn: ẹni tó béèrè owó orí, ẹ fún un ní owó orí;+ ẹni tó béèrè ìṣákọ́lẹ̀,* ẹ fún un ní ìṣákọ́lẹ̀; ẹni tí ìbẹ̀rù yẹ, ẹ bẹ̀rù rẹ̀ bó ṣe yẹ;+ ẹni tí ọlá yẹ, ẹ bọlá fún un bó ṣe yẹ.+
8 Ẹ má jẹ ẹnikẹ́ni ní gbèsè ohunkóhun, àmọ́ kí ẹ máa nífẹ̀ẹ́ ara yín;+ nítorí ẹni tó bá nífẹ̀ẹ́ ọmọnìkejì rẹ̀ ti mú òfin ṣẹ.+ 9 Nítorí àkójọ òfin tó sọ pé, “O ò gbọ́dọ̀ ṣe àgbèrè,+ o ò gbọ́dọ̀ pààyàn,+ o ò gbọ́dọ̀ jalè,+ o ò gbọ́dọ̀ ṣojúkòkòrò”+ àti àṣẹ míì tó bá wà, ni a kó pọ̀ sínú ọ̀rọ̀ yìí, pé: “Kí o nífẹ̀ẹ́ ọmọnìkejì rẹ bí ara rẹ.”+ 10 Ìfẹ́ kì í ṣiṣẹ́ ibi sí ọmọnìkejì ẹni;+ torí náà, ìfẹ́ ni àkójá òfin.+
11 Kí ẹ ṣe èyí nítorí ẹ mọ àsìkò tí a wà, pé wákàtí ti tó fún yín láti jí lójú oorun,+ torí ní báyìí, ìgbàlà wa ti sún mọ́lé ju ti ìgbà tí a di onígbàgbọ́. 12 Òru ti lọ jìnnà; ilẹ̀ ti fẹ́rẹ̀ẹ́ mọ́. Torí náà, ẹ jẹ́ ká ju àwọn iṣẹ́ tó jẹ́ ti òkùnkùn nù,+ ká sì gbé àwọn ohun ìjà ìmọ́lẹ̀ wọ̀.+ 13 Ẹ jẹ́ ká máa rìn lọ́nà tó bójú mu+ bí ìgbà téèyàn ń rìn ní ọ̀sán, kì í ṣe nínú àwọn àríyá aláriwo àti ìmutípara, kì í ṣe nínú ìṣekúṣe àti ìwà àìnítìjú,*+ kì í ṣe nínú wàhálà àti owú.+ 14 Àmọ́, ẹ gbé Olúwa Jésù Kristi wọ̀,+ ẹ má sì máa gbèrò àwọn ìfẹ́ ti ara.+
14 Ẹ tẹ́wọ́ gba ẹni tí ìgbàgbọ́ rẹ̀ kò lágbára,+ àmọ́ ẹ má ṣe dá a lẹ́jọ́ nítorí èrò rẹ̀.* 2 Ìgbàgbọ́ ẹnì kan lè fàyè gbà á láti jẹ ohun gbogbo, àmọ́ ẹni tí ìgbàgbọ́ rẹ̀ kò lágbára máa ń jẹ àwọn nǹkan ọ̀gbìn nìkan. 3 Kí ẹni tó ń jẹ má fojú àbùkù wo ẹni tí kò jẹ, kí ẹni tí kò jẹ má sì dá ẹni tó ń jẹ lẹ́jọ́,+ nítorí Ọlọ́run ti tẹ́wọ́ gba onítọ̀hún. 4 Ta ni ọ́, tí o fi ń ṣèdájọ́ ìránṣẹ́ ẹlòmíì?+ Ọ̀gá rẹ̀ ló máa pinnu bóyá ó máa ṣubú tàbí ó máa wà ní ìdúró.+ Ní tòótọ́, a máa mú un dúró, nítorí Jèhófà* lè mú un dúró.
5 Ẹnì kan gbà pé ọjọ́ kan ṣe pàtàkì ju òmíràn lọ;+ ẹlòmíì gbà pé ọjọ́ kan kò yàtọ̀ sí gbogbo ọjọ́ yòókù;+ kí èrò kálukú dá a lójú hán-ún hán-ún. 6 Ẹni tó ń pa ọjọ́ kan mọ́ ń pa á mọ́ fún Jèhófà.* Bákan náà, ẹni tó ń jẹun, ń jẹun fún Jèhófà,* nítorí ó ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run;+ ẹni tí kò sì jẹun kò jẹun fún Jèhófà,* síbẹ̀, ó ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run.+ 7 Kò sí ìkankan nínú wa, ní ti gidi, tó wà láàyè nítorí ara rẹ̀,+ kò sì sí ẹni tó kú nítorí ara rẹ̀. 8 Nítorí pé tí a bá wà láàyè, a wà láàyè fún Jèhófà,*+ tí a bá sì kú, a kú fún Jèhófà.* Torí náà, tí a bá wà láàyè tàbí tí a bá kú, a jẹ́ ti Jèhófà.*+ 9 Torí èyí ni Kristi fi kú, tí ó sì pa dà wà láàyè, kí ó lè jẹ́ Olúwa lórí àwọn òkú àti àwọn alààyè.+
10 Àmọ́ kí ló dé tí o fi ń dá arákùnrin rẹ lẹ́jọ́?+ Tàbí kí ló dé tí ò ń fojú àbùkù wo arákùnrin rẹ? Nítorí gbogbo wa la máa dúró níwájú ìjókòó ìdájọ́ Ọlọ́run.+ 11 Nítorí ó ti wà lákọsílẹ̀ pé: “‘Bí mo ti wà láàyè,’+ ni Jèhófà* wí, ‘gbogbo eékún máa tẹ̀ ba fún mi, gbogbo ahọ́n máa jẹ́wọ́ ní gbangba pé èmi ni Ọlọ́run.’”+ 12 Nítorí náà, kálukú wa ló máa jíhìn ara rẹ̀ fún Ọlọ́run.+
13 Torí náà, kí a má ṣe máa dá ara wa lẹ́jọ́ mọ́,+ kàkà bẹ́ẹ̀, ẹ pinnu pé ẹ ò ní fi ohun ìkọ̀sẹ̀ tàbí ohun ìdènà síwájú arákùnrin yín.+ 14 Mo mọ̀, ó sì dá mi lójú nínú Jésù Olúwa pé kò sí nǹkan kan tí ó jẹ́ aláìmọ́ fúnra rẹ̀;+ àmọ́ tí ẹnì kan bá ka ohun kan sí aláìmọ́, ó máa jẹ́ aláìmọ́ lójú rẹ̀. 15 Nítorí bí o bá ṣẹ arákùnrin rẹ torí oúnjẹ, o ò rìn lọ́nà tó bá ìfẹ́ mu mọ́.+ Má fi oúnjẹ rẹ pa ẹni tí Kristi kú fún run.*+ 16 Nítorí náà, ẹ má ṣe jẹ́ kí wọ́n máa sọ̀rọ̀ nípa ohun rere tí ẹ̀ ń ṣe pé ibi ni. 17 Nítorí Ìjọba Ọlọ́run kò ní nǹkan kan ṣe pẹ̀lú jíjẹ àti mímu,+ àmọ́ ó ní í ṣe pẹ̀lú òdodo àti àlàáfíà àti ayọ̀ pẹ̀lú ẹ̀mí mímọ́. 18 Nítorí ẹni tó bá ń ṣẹrú fún Kristi lọ́nà yìí ní ìtẹ́wọ́gbà Ọlọ́run, ó sì ní ìtẹ́wọ́gbà lọ́dọ̀ àwọn èèyàn.
19 Nítorí náà, ẹ jẹ́ kí a máa lépa àwọn ohun tó ń mú kí àlàáfíà wà+ àti àwọn ohun tó ń gbé ẹnì kejì wa ró.+ 20 Ẹ má ṣe máa ya iṣẹ́ Ọlọ́run lulẹ̀ nítorí oúnjẹ.+ Lóòótọ́, ohun gbogbo ni ó mọ́, àmọ́ nǹkan burúkú ni* fún ẹni tó ń jẹ oúnjẹ tó máa fa ìkọ̀sẹ̀.+ 21 Ohun tó dáa jù ni pé kéèyàn má jẹ ẹran tàbí kó má mu ọtí tàbí kó má ṣe ohunkóhun tó máa mú arákùnrin rẹ̀ kọsẹ̀.+ 22 Ìgbàgbọ́ tí o ní, jẹ́ kó wà láàárín ìwọ àti Ọlọ́run. Aláyọ̀ ni ẹni tí kì í dá ara rẹ̀ lẹ́jọ́ lórí ohun tó tẹ́wọ́ gbà. 23 Àmọ́ tó bá ń ṣiyèméjì, a ti dá a lẹ́bi tó bá jẹ ẹ́, nítorí kò jẹ ẹ́ pẹ̀lú ìgbàgbọ́. Ní tòótọ́, gbogbo ohun tí kò bá ti bá ìgbàgbọ́ mu jẹ́ ẹ̀ṣẹ̀.
15 Àmọ́ o, ó yẹ kí àwa tí a lókun máa ru àìlera àwọn tí kò lókun,+ ká má sì máa ṣe ohun tó wù wá.+ 2 Kí kálukú wa máa ṣe ohun tó wu ọmọnìkejì rẹ̀ fún ire rẹ̀, láti gbé e ró.+ 3 Nítorí Kristi pàápàá kò ṣe ohun tó wù ú,+ bó ṣe wà lákọsílẹ̀ pé: “Ẹ̀gàn ẹnu àwọn tó ń pẹ̀gàn rẹ sì ti wá sórí mi.”+ 4 Nítorí gbogbo ohun tí a kọ ní ìṣáájú ni a kọ fún wa láti gba ẹ̀kọ́,+ kí a lè ní ìrètí+ nípasẹ̀ ìfaradà+ wa àti nípasẹ̀ ìtùnú látinú Ìwé Mímọ́. 5 Ní báyìí, kí Ọlọ́run tó ń fúnni ní ìfaradà àti ìtùnú jẹ́ kí ẹ ní èrò kan náà pẹ̀lú Kristi Jésù láàárín ara yín, 6 kí ẹ lè jọ+ máa fi ohùn* kan yin Ọlọ́run àti Baba Olúwa wa Jésù Kristi lógo.
7 Nítorí náà, ẹ tẹ́wọ́ gba* ara yín,+ gẹ́gẹ́ bí Kristi pẹ̀lú ṣe tẹ́wọ́ gbà yín,+ kó lè yọrí sí ògo fún Ọlọ́run. 8 Nítorí mo sọ fún yín pé Kristi di òjíṣẹ́ àwọn tó dádọ̀dọ́*+ nítorí pé Ọlọ́run jẹ́ olóòótọ́, kí ó lè fìdí ìlérí tí Ó ṣe fún àwọn baba ńlá+ wọn múlẹ̀, 9 kí àwọn orílẹ̀-èdè sì lè yin Ọlọ́run lógo nítorí àánú rẹ̀.+ Gẹ́gẹ́ bó ṣe wà lákọsílẹ̀ pé: “Ìdí nìyẹn tí màá fi yìn ọ́ ní gbangba láàárín àwọn orílẹ̀-èdè, tí màá sì fi orin yin orúkọ rẹ.”+ 10 Ó tún sọ pé: “Ẹ bá àwọn èèyàn rẹ̀ yọ̀, ẹ̀yin orílẹ̀-èdè.”+ 11 Àti pé: “Ẹ yin Jèhófà,* gbogbo ẹ̀yin orílẹ̀-èdè, kí gbogbo àwọn èèyàn sì yìn ín.”+ 12 Àìsáyà tún sọ pé: “Gbòǹgbò Jésè yóò wà,+ ẹni tó máa dìde láti ṣàkóso àwọn orílẹ̀-èdè;+ òun ni àwọn orílẹ̀-èdè yóò ní ìrètí nínú rẹ̀.”+ 13 Kí Ọlọ́run tó ń fúnni ní ìrètí fi gbogbo ayọ̀ àti àlàáfíà kún inú yín nítorí ẹ̀ ń gbẹ́kẹ̀ lé e, kí ìrètí yín lè túbọ̀ dájú* nípasẹ̀ agbára ẹ̀mí mímọ́.+
14 Ní tèmi, ó dá mi lójú, ẹ̀yin ará mi, pé ẹ máa ń ṣe rere, ẹ ní gbogbo ìmọ̀, ẹ sì lè máa tọ́ ara yín sọ́nà.* 15 Àmọ́ ṣá, mo ti kọ̀wé sí yín lọ́nà tó túbọ̀ ṣe ṣàkó lórí àwọn kókó kan, kí n lè tún rán yín létí, nítorí inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí tí Ọlọ́run fún mi, 16 kí n lè jẹ́ ìránṣẹ́ gbogbo èèyàn tí Kristi Jésù ti yàn fún àwọn orílẹ̀-èdè.+ Mò ń ṣe iṣẹ́ mímọ́ ti ìhìn rere Ọlọ́run,+ kí àwọn orílẹ̀-èdè náà lè jẹ́ ọrẹ tí a tẹ́wọ́ gbà, tí a sì fi ẹ̀mí mímọ́ yà sọ́tọ̀.
17 Nítorí náà, ìdí wà fún mi láti yọ̀ nínú Kristi Jésù lórí àwọn ohun tó jẹ mọ́ ti Ọlọ́run. 18 Torí pé mi ò ní sọ nǹkan míì àfi àwọn ohun tí Kristi ti ṣe nípasẹ̀ mi kí àwọn orílẹ̀-èdè lè wá di onígbọràn, nípa ọ̀rọ̀ àti ìṣe mi, 19 pẹ̀lú agbára àwọn iṣẹ́ àmì àti iṣẹ́ ìyanu,*+ pẹ̀lú agbára ẹ̀mí Ọlọ́run, tó fi jẹ́ pé láti Jerúsálẹ́mù títí mo fi lọ yí ká dé Ílíríkónì ni mo ti wàásù ìhìn rere nípa Kristi+ kúnnákúnná. 20 Ní tòótọ́, lọ́nà yìí, mo ní in lọ́kàn pé mi ò ní kéde ìhìn rere níbi tí àwọn èèyàn bá ti mọ orúkọ Kristi, kí n má lọ máa kọ́lé sórí ìpìlẹ̀ ẹlòmíì; 21 gẹ́gẹ́ bó ṣe wà lákọsílẹ̀ pé: “Àwọn tí kò gbọ́ ìròyìn nípa rẹ̀ yóò rí i, àwọn tí kò sì tíì gbọ́ yóò lóye.”+
22 Ìdí nìyí tí a kò fi gbà mí láyè lọ́pọ̀ ìgbà láti wá sí ọ̀dọ̀ yín. 23 Àmọ́ ní báyìí mi ò ní ìpínlẹ̀ tí a kò tíì fọwọ́ kàn ní àwọn agbègbè yìí mọ́, ọ̀pọ̀ ọdún* ló sì ti ń wù mí kí n wá sọ́dọ̀ yín. 24 Torí náà, nígbà tí mo bá lọ sí Sípéènì, mo retí pé màá rí yín, ẹ ó sì sìn mí dójú ọ̀nà lẹ́yìn tí mo bá ti kọ́kọ́ gbádùn ìbákẹ́gbẹ́ yín fúngbà díẹ̀. 25 Àmọ́ ní báyìí, mo fẹ́ rìnrìn àjò lọ sí Jerúsálẹ́mù láti ṣe ìránṣẹ́ fún àwọn ẹni mímọ́.+ 26 Nítorí ó ti ń wu àwọn tó wà ní Makedóníà àti Ákáyà láti fi lára àwọn nǹkan wọn ṣe ìtìlẹ́yìn fún àwọn aláìní tó wà lára àwọn ẹni mímọ́ ní Jerúsálẹ́mù.+ 27 Lóòótọ́, ó wù wọ́n láti ṣe bẹ́ẹ̀, torí ní ti gidi, wọ́n jẹ wọ́n ní gbèsè; nítorí bí àwọn orílẹ̀-èdè bá ti pín nínú àwọn nǹkan tẹ̀mí wọn, àwọn náà jẹ wọ́n ní gbèsè láti fi àwọn nǹkan tara tí wọ́n ní ṣe ìtìlẹ́yìn fún wọn.+ 28 Nítorí náà, tí mo bá ti parí èyí, tí mo sì fi ìtìlẹ́yìn* yìí jíṣẹ́ fún wọn láìséwu, màá gba ọ̀dọ̀ yín lọ sí Sípéènì. 29 Yàtọ̀ síyẹn, mo mọ̀ pé nígbà tí mo bá wá sọ́dọ̀ yín, màá wá pẹ̀lú ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìbùkún látọ̀dọ̀ Kristi.
30 Ní báyìí, mo rọ̀ yín, ẹ̀yin ará, nípasẹ̀ Olúwa wa Jésù Kristi àti nípasẹ̀ ìfẹ́ tí ẹ̀mí mú kí ẹ ní, pé kí a jọ tẹra mọ́ àdúrà gbígbà sí Ọlọ́run nítorí mi,+ 31 kí a lè gbà mí+ lọ́wọ́ àwọn aláìgbàgbọ́ ní Jùdíà, kí iṣẹ́ òjíṣẹ́ mi lórí Jerúsálẹ́mù sì lè ṣe ìtẹ́wọ́gbà fún àwọn ẹni mímọ́,+ 32 kó lè jẹ́ pé nípa ìfẹ́ Ọlọ́run, màá wá sọ́dọ̀ yín tayọ̀tayọ̀, ara á sì tù mí pẹ̀lú yín. 33 Kí Ọlọ́run tó ń fúnni ní àlàáfíà wà pẹ̀lú gbogbo yín.+ Àmín.
16 Mo fẹ́ kí ẹ mọ* Fébè arábìnrin wa, tó jẹ́ òjíṣẹ́ ní ìjọ tó wà ní Kẹnkíríà,+ 2 kí ẹ lè tẹ́wọ́ gbà á nínú Olúwa lọ́nà tó yẹ àwọn ẹni mímọ́, kí ẹ sì ràn án lọ́wọ́ nínú ohun tó bá nílò,+ torí òun fúnra rẹ̀ ti gbèjà ọ̀pọ̀ èèyàn, títí kan èmi náà.
3 Ẹ bá mi kí Pírísíkà àti Ákúílà,+ àwọn tí a jọ ń ṣiṣẹ́ Kristi Jésù, 4 àwọn tí wọ́n fi ẹ̀mí* ara wọn wewu nítorí mi,*+ kì í ṣe èmi nìkan ló ń dúpẹ́ lọ́wọ́ wọn, gbogbo ìjọ àwọn orílẹ̀-èdè pátá náà ń dúpẹ́. 5 Bákan náà, ẹ kí ìjọ tó wà ní ilé wọn.+ Ẹ kí Épénétù àyànfẹ́ mi, tó jẹ́ àkọ́so ní Éṣíà fún Kristi. 6 Ẹ kí Màríà, tó ti ṣiṣẹ́ kára fún yín. 7 Ẹ kí Andironíkọ́sì àti Júníásì, àwọn ìbátan mi,+ tí a jọ ṣẹ̀wọ̀n, àwọn tí àwọn àpọ́sítélì mọ̀ dáadáa, tí wọ́n sì ti pẹ́ jù mí lọ nínú Kristi.
8 Ẹ bá mi kí Áńpílíátù, àyànfẹ́ mi nínú Olúwa. 9 Ẹ kí Úbánọ́sì, tí a jọ ń ṣiṣẹ́ Kristi àti Sítákísì àyànfẹ́ mi. 10 Ẹ kí Ápélésì, ẹni ìtẹ́wọ́gbà nínú Kristi. Ẹ kí àwọn tó wà ní agbo ilé Àrísítóbúlù. 11 Ẹ kí Hẹ́ródíónì, ìbátan mi. Ẹ kí àwọn tó wà nínú Olúwa ní agbo ilé Nákísọ́sì. 12 Ẹ kí Tírífénà àti Tírífósà, àwọn obìnrin tó ń ṣiṣẹ́ kára nínú Olúwa. Ẹ kí Pésísì, àyànfẹ́ wa, torí ó ti ṣiṣẹ́ kára nínú Olúwa. 13 Ẹ kí Rúfọ́ọ̀sì àyànfẹ́ nínú Olúwa àti ìyá rẹ̀, tó tún jẹ́ ìyá mi. 14 Ẹ kí Asinkirítọ́sì, Fílégónì, Hẹ́mísì, Pátíróbásì, Hẹ́másì àti àwọn ará tó wà pẹ̀lú wọn. 15 Ẹ kí Fílólógọ́sì àti Júlíà, Néréúsì àti arábìnrin rẹ̀ àti Òlíńpásì pẹ̀lú gbogbo ẹni mímọ́ tó wà pẹ̀lú wọn. 16 Ẹ fi ìfẹnukonu mímọ́ kí ara yín. Gbogbo àwọn ìjọ Kristi kí yín.
17 Ní báyìí, ẹ̀yin ará, mo rọ̀ yín pé kí ẹ máa ṣọ́ àwọn tó ń fa ìyapa àti ìkọ̀sẹ̀ tó lòdì sí ẹ̀kọ́ tí ẹ ti kọ́, kí ẹ sì yẹra fún wọn.+ 18 Nítorí irú àwọn èèyàn bẹ́ẹ̀ kì í ṣe ẹrú Olúwa wa Kristi, bí kò ṣe ti ohun tí wọ́n fẹ́ jẹ,* wọ́n máa ń fi ọ̀rọ̀ dídùn àti ọ̀rọ̀ ìpọ́nni fa ọkàn àwọn tí kò fura mọ́ra. 19 Gbogbo èèyàn ti gbọ́ nípa ìgbọràn yín, torí náà, inú mi ń dùn nítorí yín. Àmọ́ mo fẹ́ kí ẹ jẹ́ ọlọ́gbọ́n ní ti ohun rere, ṣùgbọ́n aláìmọ̀kan ní ti ohun búburú.+ 20 Ní tirẹ̀, Ọlọ́run tó ń fúnni ní àlàáfíà máa mú kí ẹsẹ̀ yín tẹ Sátánì rẹ́+ láìpẹ́. Kí inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Olúwa wa Jésù wà pẹ̀lú yín.
21 Tímótì, tí a jọ ń ṣiṣẹ́, kí yín, Lúkíọ́sì àti Jásónì pẹ̀lú Sósípátérì, àwọn ìbátan mi+ náà kí yín.
22 Èmi, Tẹ́tíọ́sì, tí mo kọ lẹ́tà yìí, kí yín nínú Olúwa.
23 Gáyọ́sì,+ tó gba èmi àti gbogbo ìjọ lálejò, kí yín. Érásítù, ẹni tó ń bójú tó ìṣúra ìlú,* kí yín, Kúátọ́sì, arákùnrin rẹ̀ náà kí yín. 24* ——
25 Ní báyìí, Ẹni tó lè fìdí yín múlẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìhìn rere tí mò ń kéde àti ìwàásù Jésù Kristi, gẹ́gẹ́ bí ìfihàn àṣírí mímọ́+ tí a ti pa mọ́ ní ìdákẹ́jẹ́ẹ́ látọjọ́ pípẹ́, 26 àmọ́ tí a ti fi hàn kedere* ní báyìí, ti a sì jẹ́ kí àwọn èèyàn mọ̀ ọ́n láàárín gbogbo orílẹ̀-èdè nípasẹ̀ àwọn Ìwé Mímọ́ alásọtẹ́lẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àṣẹ tí Ọlọ́run ayérayé pa pé ká fi ìgbàgbọ́ gbé ìgbọràn ga; 27 Ọlọ́run, ẹnì kan ṣoṣo tí ó gbọ́n,+ ni kí ògo nípasẹ̀ Jésù Kristi jẹ́ tirẹ̀ títí láé. Àmín.
Ní Grk., “èso.”
Tàbí “àwọn tí kì í ṣe Gíríìkì.” Ní Grk., “aláìgbédè.”
Ìyẹn, ìwà àti ìṣe.
Tàbí “àwọn ohun tó ń rákò.”
Tàbí “jọ́sìn.”
Tàbí “fi bíbá obìnrin lò pọ̀.”
Tàbí “èrè.”
Tàbí “Bí wọn ò ṣe ní ìmọ̀ tó péye nípa ẹni tí Ọlọ́run jẹ́.”
Tàbí “ìwọra.”
Ní Grk., “asọ̀rọ̀ wúyẹ́wúyẹ́.”
Tàbí “hùmọ̀ ohun tó ń ṣeni léṣe.”
Tàbí “ìpamọ́ra.”
Tàbí “ọkàn gbogbo èèyàn.”
Ní Grk., “láàárín ìrònú wọn, à ń.”
Tàbí “fi ọ̀rọ̀ ẹnu kọ́ ẹ.”
Tàbí “Ìkọlà.”
Tàbí “ìkọlà.”
Tàbí “àìkọlà.”
Tàbí “aláìkọlà.”
Tàbí “àìkọlà.”
Tàbí “ìkọlà.”
Tàbí “aláìkọlà.”
Tàbí “kọlà.”
Tàbí “ìkọlà.”
Tàbí “ìkọlà.”
Tàbí “ìkọlà?”
Tàbí “ejò gùǹte.”
Ní Grk., “ẹran ara.”
Tàbí “ètùtù; ìpadàrẹ́.”
Tàbí “ìpamọ́ra.”
Tàbí “kọlà.”
Tàbí “aláìkọlà.”
Wo Àfikún A5.
Tàbí “ohun.”
Tàbí “dárí ẹ̀ṣẹ̀ wọn jì.”
Wo Àfikún A5.
Tàbí “kọlà.”
Tàbí “aláìkọlà.”
Tàbí “kọlà.”
Tàbí “aláìkọlà.”
Tàbí “ìkọlà.”
Tàbí “ìdánilójú.”
Tàbí “aláìkọlà.”
Tàbí “kọlà.”
Tàbí “ìkọlà.”
Tàbí “aláìkọlà.”
Ní Grk., “èso.”
Ní Grk., “èso.”
Tàbí kó jẹ́, “tó ń mú kí ohun tí kò sí wà.”
Ní Grk., “èso.”
Tàbí “tó yàgàn.”
Tàbí kó jẹ́, “a wà ní àlàáfíà.”
Tàbí kó jẹ́, “à ń yọ̀.”
Tàbí kó jẹ́, “à ń yọ̀.”
Tàbí “ṣe ṣàn dé ọ̀dọ̀ ọ̀pọ̀ èèyàn!”
Tàbí “mọ́ òpó igi.” Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.
Tàbí “tú sílẹ̀; dárí jì.”
Ìyẹn, láti pa ẹ̀ṣẹ̀ rẹ́.
Tàbí “ara.”
Tàbí “ara.”
Ní Grk., “owó iṣẹ́.”
Ní Grk., “àwọn ẹ̀yà ara.”
Ní Grk., “àwọn ẹ̀yà ara.”
Ní Grk., “àwọn ẹ̀yà ara.”
Ọ̀rọ̀ Hébérù tàbí Árámáíkì tó túmọ̀ sí “Bàbá!”
Tàbí “ìrora tí a kò sọ síta.”
Ní Grk., “èso.”
Ní Grk., “èso.”
Ní Grk., “èso.”
Ní Grk., “kò sí lọ́wọ́ ẹni tó ń fẹ́ tàbí lọ́wọ́ ẹni tó ń sáré.”
Tàbí “ìkòkò.”
Wo Àfikún A5.
Ní Grk., “yóò sì gé e kúrú.” Tàbí “yóò sì mú un ṣẹ kíákíá.”
Wo Àfikún A5.
Ní Grk., “èso.”
Ní Grk., “jẹ́ ọlọ́rọ̀.”
Wo Àfikún A5.
Wo Àfikún A5.
Tàbí “ìròyìn wa?”
Ní Grk., “èso.”
Wo Àfikún A5.
Tàbí “ọkàn.”
Tàbí “gbé iṣẹ́ òjíṣẹ́ mi ga.”
Ní Grk., “ẹran ara.”
Tàbí “fọ́nnu.”
Tàbí “fọ́nnu.”
Tàbí “Olùgbàlà.”
Wo Àfikún A5.
Tàbí “àsìkò yìí.” Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.
Tàbí “yan ìgbàgbọ́ fún kálukú; pín ìgbàgbọ́ fún kálukú.”
Tàbí “gbani níyànjú.”
Tàbí “gbani níyànjú.”
Tàbí “fúnni ní nǹkan.”
Tàbí “mú ipò iwájú.”
Tàbí “lójú méjèèjì.”
Tàbí “àgàbàgebè.”
Tàbí “ẹ máa lo ìdánúṣe.”
Tàbí “Ẹ jẹ́ aláápọn; Ẹ jẹ́ onítara.”
Tàbí “Ẹ má ṣe ìmẹ́lẹ́ lẹ́nu iṣẹ́ yín.”
Wo Àfikún A5.
Tàbí “ní èrò gíga.”
Ìyẹn, ìrunú Ọlọ́run.
Wo Àfikún A5.
Ìyẹn, láti mú kí ọkàn ẹni náà rọ̀, kí inú rẹ̀ sì yọ́.
Tàbí “ọkàn.”
Tàbí “láti fìyà jẹ.”
Tàbí “owó òde.”
Tàbí “ìwà ọ̀dájú.” Ó ń tọ́ka sí ọ̀rọ̀ Gíríìkì náà, a·selʹgei·a tí wọ́n bá lò ó fún ohun tó ju ẹyọ kan lọ. Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.
Tàbí kó jẹ́, “àwọn ohun tó ń kọ ọ́ lóminú.”
Wo Àfikún A5.
Wo Àfikún A5.
Wo Àfikún A5.
Wo Àfikún A5.
Wo Àfikún A5.
Wo Àfikún A5.
Wo Àfikún A5.
Wo Àfikún A5.
Tàbí “pa ẹni tí Kristi kú fún rẹ́.”
Tàbí “àmọ́ kò tọ̀nà.”
Ní Grk., “ẹnu.”
Tàbí “ẹ gba.”
Tàbí “kọlà.”
Wo Àfikún A5.
Tàbí “kún rẹ́rẹ́.”
Tàbí “kọ́ ara yín.”
Tàbí “àwọn àmì.”
Tàbí kó jẹ́, “ọdún díẹ̀.”
Ní Grk., “èso.”
Tàbí “Mo dámọ̀ràn.”
Ní Grk., “ọrùn.”
Tàbí “ọkàn mi.”
Tàbí “ti ikùn wọn.”
Tàbí “ẹni tó jẹ́ ìríjú ìlú.”
Wo Àfikún A3.
Tàbí “tí a ṣí payá.”