ÀWỌN ỌBA KEJÌ
1 Lẹ́yìn ikú Áhábù, Móábù+ ṣọ̀tẹ̀ sí Ísírẹ́lì.
2 Nígbà náà, Ahasáyà já bọ́ láti ibi asẹ́ tó wà ní yàrá òrùlé rẹ̀ ní Samáríà, ó sì fara pa. Torí náà, ó rán àwọn òjíṣẹ́, ó sì sọ fún wọn pé: “Ẹ lọ wádìí lọ́dọ̀ Baali-sébúbù ọlọ́run Ẹ́kírónì+ bóyá ibi tí mo fi ṣèṣe yìí máa san.”+ 3 Àmọ́, áńgẹ́lì Jèhófà sọ fún Èlíjà*+ ará Tíṣíbè pé: “Gbéra, lọ pàdé àwọn òjíṣẹ́ ọba Samáríà, kí o sọ fún wọn pé, ‘Ṣé kò sí Ọlọ́run ní Ísírẹ́lì ni, tí ẹ fi ń lọ wádìí lọ́dọ̀ Baali-sébúbù ọlọ́run Ẹ́kírónì?+ 4 Nítorí náà, ohun tí Jèhófà sọ nìyí: “O ò ní kúrò lórí ibùsùn tí o wà yìí, torí ó dájú pé wàá kú.”’” Èlíjà sì bá tirẹ̀ lọ.
5 Nígbà tí àwọn òjíṣẹ́ náà pa dà sọ́dọ̀ rẹ̀, lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, ó béèrè lọ́wọ́ wọn pé: “Kí ló dé tí ẹ fi pa dà?” 6 Wọ́n dá a lóhùn pé: “Ọkùnrin kan wá pàdé wa, ó sọ fún wa pé, ‘Ẹ pa dà sọ́dọ̀ ọba tó rán yín, kí ẹ sì sọ fún un pé, “Ohun tí Jèhófà sọ nìyí: ‘Ṣé kò sí Ọlọ́run ní Ísírẹ́lì ni, tí o fi ní kí wọ́n lọ wádìí lọ́dọ̀ Baali-sébúbù ọlọ́run Ẹ́kírónì? Nítorí náà, o ò ní kúrò lórí ibùsùn tí o wà yìí, torí ó dájú pé wàá kú.’”’”+ 7 Ó wá béèrè lọ́wọ́ wọn pé: “Báwo ni ọkùnrin tó wá pàdé yín, tó sọ ọ̀rọ̀ yìí fún yín ṣe rí?” 8 Torí náà, wọ́n sọ fún un pé: “Ọkùnrin náà wọ aṣọ onírun,+ ó sì de àmùrè awọ mọ́ ìbàdí rẹ̀.”+ Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, ó sọ pé: “Èlíjà ará Tíṣíbè ni.”
9 Ọba wá rán olórí àádọ́ta (50) ọmọ ogun sí i pẹ̀lú àádọ́ta (50) ọkùnrin rẹ̀. Nígbà tó lọ bá Èlíjà, ó rí i tó jókòó sórí òkè. Ó sọ fún un pé: “Èèyàn Ọlọ́run tòótọ́,+ ọba sọ pé, ‘Sọ̀ kalẹ̀ wá.’” 10 Àmọ́ Èlíjà dá olórí àádọ́ta (50) ọmọ ogun náà lóhùn pé: “Ó dáa, tó bá jẹ́ pé èèyàn Ọlọ́run ni mí lóòótọ́, kí iná bọ́ láti ọ̀run,+ kó sì jó ìwọ àti àádọ́ta (50) ọkùnrin rẹ run.” Ni iná bá bọ́ láti ọ̀run, ó sì jó òun àti àádọ́ta (50) ọkùnrin rẹ̀ run.
11 Nítorí náà, ọba tún rán olórí àádọ́ta (50) ọmọ ogun míì sí i pẹ̀lú àádọ́ta (50) ọkùnrin rẹ̀. Ó lọ, ó sì sọ fún un pé: “Èèyàn Ọlọ́run tòótọ́, ohun tí ọba sọ nìyí, ‘Sọ̀ kalẹ̀ wá kíákíá.’” 12 Àmọ́ Èlíjà dá wọn lóhùn pé: “Tó bá jẹ́ pé èèyàn Ọlọ́run tòótọ́ ni mí lóòótọ́, kí iná bọ́ láti ọ̀run, kó sì jó ìwọ àti àádọ́ta (50) ọkùnrin rẹ run.” Ni iná Ọlọ́run bá bọ́ láti ọ̀run, ó sì jó òun àti àádọ́ta (50) ọkùnrin rẹ̀ run.
13 Lẹ́yìn náà, ọba rán olórí àádọ́ta (50) ọmọ ogun kẹta sí i pẹ̀lú àádọ́ta (50) ọkùnrin rẹ̀. Àmọ́ olórí àádọ́ta (50) ọmọ ogun kẹta jáde lọ, ó sì tẹrí ba lórí ìkúnlẹ̀ níwájú Èlíjà, ó bẹ̀rẹ̀ sí í bẹ̀ ẹ́ pé kó ṣojú rere sí òun, ó ní: “Èèyàn Ọlọ́run tòótọ́, jọ̀wọ́, jẹ́ kí ẹ̀mí mi àti ẹ̀mí* àádọ́ta (50) ìránṣẹ́ rẹ yìí ṣeyebíye lójú rẹ. 14 Iná ti bọ́ láti ọ̀run, ó sì ti jó àwọn olórí àádọ́ta (50) ọmọ ogun méjì tó ṣáájú run pẹ̀lú àádọ́ta (50) wọn, ṣùgbọ́n ní báyìí, jẹ́ kí ẹ̀mí* mi ṣeyebíye lójú rẹ.”
15 Áńgẹ́lì Jèhófà wá sọ fún Èlíjà pé: “Sọ̀ kalẹ̀ tẹ̀ lé e. Má bẹ̀rù rẹ̀.” Torí náà, ó dìde, ó sọ̀ kalẹ̀, ó sì tẹ̀ lé e lọ sọ́dọ̀ ọba. 16 Èlíjà wá sọ fún ọba pé, “Ohun tí Jèhófà sọ nìyí: ‘O rán àwọn òjíṣẹ́ pé kí wọ́n lọ wádìí lọ́dọ̀ Baali-sébúbù ọlọ́run Ẹ́kírónì.+ Ṣé kò sí Ọlọ́run ní Ísírẹ́lì ni?+ Kí ló dé tí o ò fi wádìí lọ́dọ̀ rẹ̀? Torí náà, o ò ní kúrò lórí ibùsùn tí o wà yìí, torí ó dájú pé wàá kú.’” 17 Torí náà, ó kú, gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ tí Jèhófà gbẹnu Èlíjà sọ. Àmọ́ torí pé kò ní ọmọkùnrin kankan, Jèhórámù*+ jọba ní ipò rẹ̀, ní ọdún kejì Jèhórámù+ ọmọ Jèhóṣáfátì ọba Júdà.
18 Ní ti ìyókù ìtàn Ahasáyà+ àti ohun tí ó ṣe, ǹjẹ́ kò wà lákọsílẹ̀ nínú ìwé ìtàn ìgbà àwọn ọba Ísírẹ́lì?
2 Nígbà tó kù díẹ̀ tí Jèhófà máa fi ìjì+ gbé Èlíjà+ lọ sí ọ̀run,* Èlíjà àti Èlíṣà+ jáde kúrò ní Gílígálì.+ 2 Èlíjà sọ fún Èlíṣà pé: “Jọ̀ọ́, dúró sí ibí yìí, nítorí pé Jèhófà ti rán mi lọ sí Bẹ́tẹ́lì.” Àmọ́ Èlíṣà sọ pé: “Bí Jèhófà ti wà láàyè, tí ìwọ náà* sì wà láàyè, mi ò ní fi ọ́ sílẹ̀.” Nítorí náà, wọ́n lọ sí Bẹ́tẹ́lì.+ 3 Ìgbà náà ni àwọn ọmọ wòlíì* ní Bẹ́tẹ́lì jáde wá bá Èlíṣà, wọ́n sì sọ fún un pé: “Ṣé o mọ̀ pé òní ni Jèhófà máa mú ọ̀gá rẹ lọ, tí kò sì ní ṣe olórí rẹ mọ́?”+ Ó dá wọn lóhùn pé: “Mo mọ̀. Ẹ dákẹ́.”
4 Èlíjà wá sọ fún un pé: “Èlíṣà, jọ̀ọ́ dúró sí ibí yìí, nítorí pé, Jèhófà ti rán mi lọ sí Jẹ́ríkò.”+ Àmọ́ ó sọ pé: “Bí Jèhófà ti wà láàyè, tí ìwọ náà* sì wà láàyè, mi ò ní fi ọ́ sílẹ̀.” Nítorí náà, wọ́n lọ sí Jẹ́ríkò. 5 Àwọn ọmọ wòlíì tó wà ní Jẹ́ríkò wá bá Èlíṣà, wọ́n sì sọ fún un pé: “Ṣé o mọ̀ pé òní ni Jèhófà máa mú ọ̀gá rẹ lọ, tí kò sì ní ṣe olórí rẹ mọ́?” Ó dá wọn lóhùn pé: “Mo mọ̀. Ẹ dákẹ́.”
6 Èlíjà wá sọ fún un pé: “Jọ̀ọ́, dúró sí ibí yìí, nítorí pé Jèhófà ti rán mi lọ sí Jọ́dánì.” Àmọ́ ó sọ pé: “Bí Jèhófà ti wà láàyè, tí ìwọ náà* sì wà láàyè, mi ò ní fi ọ́ sílẹ̀.” Nítorí náà, àwọn méjèèjì jọ ń lọ. 7 Bákan náà, àádọ́ta (50) lára àwọn ọmọ wòlíì jáde lọ, wọ́n dúró lọ́ọ̀ọ́kán, wọ́n sì ń wo àwọn méjèèjì bí wọ́n ṣe dúró lẹ́gbẹ̀ẹ́ Jọ́dánì. 8 Nígbà náà, Èlíjà mú ẹ̀wù oyè rẹ̀,+ ó ká a, ó sì lu omi náà, ó pín sápá ọ̀tún àti sápá òsì, tó fi jẹ́ pé àwọn méjèèjì gba orí ilẹ̀ gbígbẹ sọdá.+
9 Gẹ́rẹ́ lẹ́yìn tí wọ́n sọdá, Èlíjà sọ fún Èlíṣà pé: “Béèrè ohun tí o bá fẹ́ kí n ṣe fún ọ kí Ọlọ́run tó mú mi kúrò lọ́dọ̀ rẹ.” Torí náà, Èlíṣà sọ pé: “Jọ̀ọ́, fún mi ní ìpín*+ méjì nínú ẹ̀mí rẹ.”+ 10 Ó fèsì pé: “Ohun tí o béèrè yìí kò rọrùn. Tí o bá rí mi nígbà tí Ọlọ́run bá mú mi kúrò lọ́dọ̀ rẹ, á rí bẹ́ẹ̀ fún ọ; àmọ́ tí o ò bá rí mi, kò ní rí bẹ́ẹ̀.”
11 Bí wọ́n ṣe ń rìn lọ, wọ́n ń sọ̀rọ̀, lójijì kẹ̀kẹ́ ẹṣin oníná àti àwọn ẹṣin oníná+ ya àwọn méjèèjì sọ́tọ̀, ìjì sì gbé Èlíjà lọ sí ọ̀run.*+ 12 Bí Èlíṣà ṣe ń wò ó, ó ké jáde pé: “Bàbá mi, bàbá mi! Kẹ̀kẹ́ ẹṣin Ísírẹ́lì àti àwọn agẹṣin rẹ̀!”+ Nígbà tí kò rí i mọ́, ó di ẹ̀wù ara rẹ̀ mú, ó sì fà á ya sí méjì.+ 13 Lẹ́yìn náà, ó mú ẹ̀wù oyè+ Èlíjà tó já bọ́ lára rẹ̀, ó pa dà, ó sì dúró lẹ́gbẹ̀ẹ́ etí odò Jọ́dánì. 14 Ló bá mú ẹ̀wù oyè Èlíjà tó já bọ́ lára rẹ̀, ó fi lu omi náà, ó sì sọ pé: “Jèhófà Ọlọ́run Èlíjà dà?” Nígbà tó lu omi náà, ó pín sí apá ọ̀tún àti sí apá òsì, tí Èlíṣà fi lè sọdá.+
15 Nígbà tí àwọn ọmọ wòlíì tó wà ní Jẹ́ríkò rí i lókèèrè, wọ́n sọ pé: “Ẹ̀mí Èlíjà ti bà lé Èlíṣà.”+ Torí náà, wọ́n wá pàdé rẹ̀, wọ́n sì tẹrí ba mọ́lẹ̀ níwájú rẹ̀. 16 Wọ́n sọ fún un pé: “Àádọ́ta (50) géńdé ọkùnrin wà níbí pẹ̀lú àwọn ìránṣẹ́ rẹ. Jọ̀ọ́, jẹ́ kí wọ́n lọ wá ọ̀gá rẹ. Ó lè jẹ́ pé, nígbà tí ẹ̀mí* Jèhófà gbé e, orí ọ̀kan nínú àwọn òkè tàbí àwọn àfonífojì ni ó jù ú sí.”+ Àmọ́ ó sọ pé: “Ẹ má ṣe rán wọn.” 17 Síbẹ̀, wọ́n ń rọ̀ ọ́ ṣáá títí ó fi sú u, torí náà ó ní: “Ẹ rán wọn lọ.” Wọ́n wá rán àádọ́ta (50) ọkùnrin, ọjọ́ mẹ́ta ni wọ́n sì fi wá a, ṣùgbọ́n wọn ò rí i. 18 Nígbà tí wọ́n pa dà sọ́dọ̀ rẹ̀, ó ṣì wà ní Jẹ́ríkò.+ Ó wá sọ fún wọn pé: “Ṣé mi ò sọ fún yín pé kí ẹ má lọ?”
19 Nígbà tó yá, àwọn ọkùnrin ìlú náà sọ fún Èlíṣà pé: “Ọ̀gá wa, bí ìwọ náà ṣe mọ̀, ibi tí ìlú yìí wà dáa;+ àmọ́ omi rẹ̀ kò dáa, ilẹ̀ rẹ̀ sì ti ṣá.”* 20 Ló bá sọ pé: “Ẹ mú abọ́ kékeré tuntun kan wá, kí ẹ sì bu iyọ̀ sínú rẹ̀.” Nítorí náà, wọ́n gbé e wá fún un. 21 Ó wá lọ sí orísun omi náà, ó da iyọ̀ sínú rẹ̀,+ ó sì sọ pé: “Ohun tí Jèhófà sọ nìyí, ‘Mo ti wo omi yìí sàn. Kò ní fa ikú, kò sì ní sọni di àgàn* mọ́.’” 22 Ìwòsàn sì bá omi náà títí di òní yìí, gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ tí Èlíṣà sọ.
23 Ó gòkè láti ibẹ̀ lọ sí Bẹ́tẹ́lì. Bó ṣe ń lọ lójú ọ̀nà, àwọn ọmọkùnrin kan jáde wá láti inú ìlú náà, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í fi ṣe yẹ̀yẹ́,+ wọ́n ń sọ fún un pé: “Gòkè lọ, apárí! Gòkè lọ, apárí!” 24 Níkẹyìn, ó bojú wẹ̀yìn, ó wò wọ́n, ó sì gégùn-ún fún wọn ní orúkọ Jèhófà. Ni abo bíárì+ méjì bá jáde láti inú igbó, wọ́n sì fa méjìlélógójì (42) lára àwọn ọmọ náà ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ.+ 25 Ó kúrò níbẹ̀ lọ sí Òkè Kámẹ́lì,+ láti ibẹ̀, ó pa dà sí Samáríà.
3 Jèhórámù+ ọmọ Áhábù di ọba lórí Ísírẹ́lì ní Samáríà ní ọdún kejìdínlógún Jèhóṣáfátì ọba Júdà, ọdún méjìlá (12) ló sì fi ṣàkóso. 2 Ó ń ṣe ohun tó burú lójú Jèhófà, àmọ́ kò ṣe tó ohun tí bàbá àti ìyá rẹ̀ ṣe, nítorí ó mú ọwọ̀n òrìṣà Báálì tí bàbá rẹ̀ ṣe kúrò.+ 3 Síbẹ̀, àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tí Jèróbóámù ọmọ Nébátì mú kí Ísírẹ́lì dá ni òun náà ń dá.+ Kò jáwọ́ nínú wọn.
4 Nígbà náà, Méṣà ọba Móábù máa ń sin àgùntàn, ó sì máa ń fi ọ̀kẹ́ márùn-ún (100,000) ọ̀dọ́ àgùntàn àti ọ̀kẹ́ márùn-ún (100,000) akọ àgùntàn tí a kò rẹ́ irun wọn san ìṣákọ́lẹ̀* fún ọba Ísírẹ́lì. 5 Kété lẹ́yìn ikú Áhábù,+ ọba Móábù ṣọ̀tẹ̀ sí ọba Ísírẹ́lì.+ 6 Nítorí náà, Ọba Jèhórámù jáde ní Samáríà lákòókò yẹn, ó sì pe gbogbo Ísírẹ́lì jọ. 7 Ó tún ránṣẹ́ sí Jèhóṣáfátì ọba Júdà pé: “Ọba Móábù ti ṣọ̀tẹ̀ sí mi. Ṣé wàá tẹ̀ lé mi, ká lọ bá Móábù jà?” Ó dáhùn pé: “Màá tẹ̀ lé ọ.+ Ìkan náà ni èmi àti ìwọ. Ìkan náà ni àwọn èèyàn mi àti àwọn èèyàn rẹ. Ìkan náà sì ni àwọn ẹṣin mi àti àwọn ẹṣin rẹ.”+ 8 Ó wá béèrè pé: “Ọ̀nà wo ni ká gbà lọ?” Ó dáhùn pé: “Ọ̀nà aginjù Édómù.”
9 Ọba Ísírẹ́lì bá gbéra pẹ̀lú ọba Júdà àti ọba Édómù.+ Lẹ́yìn tí wọ́n ti fi ọjọ́ méje rìn yí ká, kò sí omi tí àwọn tó wà ní ibùdó àti àwọn ẹran ọ̀sìn tó wà pẹ̀lú wọn máa mu. 10 Ọba Ísírẹ́lì wá sọ pé: “Ó mà ṣe o! Jèhófà pe àwọn ọba mẹ́ta yìí kó lè fi wọ́n lé Móábù lọ́wọ́!” 11 Ni Jèhóṣáfátì bá sọ pé: “Ṣé kò sí wòlíì Jèhófà níbí tó lè bá wa wádìí lọ́dọ̀ Jèhófà ni?”+ Torí náà, ọ̀kan lára àwọn ìránṣẹ́ ọba Ísírẹ́lì dáhùn pé: “Èlíṣà+ ọmọ Ṣáfátì, ẹni tó máa ń bu omi sí ọwọ́ Èlíjà*+ wà níbí.” 12 Lẹ́yìn náà, Jèhóṣáfátì sọ pé: “Ọ̀rọ̀ Jèhófà wà lẹ́nu rẹ̀.” Torí náà, ọba Ísírẹ́lì àti Jèhóṣáfátì àti ọba Édómù lọ bá a.
13 Èlíṣà sọ fún ọba Ísírẹ́lì pé: “Kí ló pa èmi àti ìwọ pọ̀?*+ Lọ bá àwọn wòlíì bàbá rẹ àti àwọn wòlíì ìyá rẹ.”+ Àmọ́ ọba Ísírẹ́lì sọ fún un pé: “Rárá, torí Jèhófà ló pe àwọn ọba mẹ́ta yìí kó lè fi wọ́n lé Móábù lọ́wọ́.” 14 Èlíṣà fèsì pé: “Bí Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun, ẹni tí mò ń sìn* ti wà láàyè, bí kò bá jẹ́ ti Jèhóṣáfátì+ ọba Júdà tí mo rò, mi ò tiẹ̀ ní wojú ẹ tàbí kí n fetí sí ọ.+ 15 Ní báyìí, ẹ bá mi pe ẹnì kan tó ń ta háàpù*+ wá.” Bí ẹni tó ń ta háàpù náà ṣe bẹ̀rẹ̀ sí í ta á, ẹ̀mí* Jèhófà bà lé e.+ 16 Ó sì sọ pé: “Ohun tí Jèhófà sọ nìyí: ‘Ẹ gbẹ́ àwọn kòtò sí àfonífojì yìí, 17 nítorí ohun tí Jèhófà sọ nìyí: “Ẹ kò ní rí ìjì, bẹ́ẹ̀ ni ẹ kò ní rí òjò; síbẹ̀, omi máa kún àfonífojì yìí,+ ẹ ó sì mu látinú rẹ̀, ẹ̀yin àti àwọn ẹran ọ̀sìn yín pẹ̀lú àwọn ẹran míì tí ẹ ní.”’ 18 Àmọ́ kékeré nìyẹn lójú Jèhófà,+ torí pé ó máa fi Móábù lé yín lọ́wọ́.+ 19 Kí ẹ pa gbogbo ìlú olódi run+ àti gbogbo ìlú tó dára jù lọ, gbogbo igi tó dára ni kí ẹ gé lulẹ̀, gbogbo orísun omi ni kí ẹ dí pa, gbogbo ilẹ̀ tó dára sì ni kí ẹ fi òkúta bà jẹ́.”+
20 Nígbà tó di àárọ̀, ní àsìkò tí wọ́n máa ń fi ọrẹ ọkà òwúrọ̀ rúbọ,+ ṣàdédé ni omi ń ṣàn bọ̀ láti apá Édómù, omi sì kún gbogbo ilẹ̀ náà.
21 Gbogbo àwọn ọmọ Móábù gbọ́ pé àwọn ọba náà ti wá láti bá wọn jà, torí náà, wọ́n pe gbogbo àwọn èèyàn tó lè lo nǹkan ìjà* jọ, wọ́n sì to ara wọn sójú ààlà. 22 Nígbà tí wọ́n dìde ní àárọ̀ kùtù, oòrùn ń ràn sórí omi náà, àmọ́ lójú àwọn ọmọ Móábù, ní òdìkejì, ńṣe ni omi náà pupa bí ẹ̀jẹ̀. 23 Wọ́n sọ pé: “Ẹ wo ẹ̀jẹ̀! Ó dájú pé àwọn ọba náà ti fi idà ṣá ara wọn pa. Torí náà, lọ kó ẹrù ogun,+ ìwọ Móábù!” 24 Nígbà tí wọ́n wọ ibùdó Ísírẹ́lì, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì dìde, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í pa àwọn ọmọ Móábù, tí wọ́n fi sá kúrò níwájú wọn.+ Wọ́n wọ inú Móábù, wọ́n sì ń pa àwọn ọmọ Móábù bí wọ́n ṣe ń lọ. 25 Wọ́n wó ìlú náà palẹ̀, àwọn ọkùnrin náà lọ́kọ̀ọ̀kan sì ju òkúta sórí gbogbo ilẹ̀ tó dára, títí òkúta fi kún gbogbo ilẹ̀ náà; wọ́n dí gbogbo orísun omi pa,+ wọ́n sì gé gbogbo igi tó dára lulẹ̀.+ Níkẹyìn, àwọn ògiri olókùúta Kiri-hárésétì+ nìkan ló ṣẹ́ kù ní ìdúró, àwọn tó ń ta kànnàkànnà yí i ká, wọ́n sì wó o lulẹ̀.
26 Nígbà tí ọba Móábù rí i pé apá òun ò ká ogun náà mọ́, ó kó ọgọ́rùn-ún méje (700) ọkùnrin tó ń lo idà jọ, kí wọ́n lè kọjá sọ́dọ̀ ọba Édómù;+ àmọ́ wọn ò lè kọjá. 27 Torí náà, ó mú ọmọ rẹ̀ àkọ́bí tó máa jọba ní ipò rẹ̀, ó sì fi rú ẹbọ sísun+ lórí ògiri. Wọ́n bínú sí Ísírẹ́lì gan-an, torí náà, àwọn èèyàn Ísírẹ́lì pa dà lẹ́yìn ọba Móábù, wọ́n sì pa dà sí ilẹ̀ wọn.
4 Nígbà náà, ọ̀kan lára ìyàwó àwọn ọmọ wòlíì+ sunkún lọ bá Èlíṣà, ó ní: “Ìránṣẹ́ rẹ, ọkọ mi, ti kú, o sì mọ̀ pé gbogbo ọjọ́ ayé ìránṣẹ́ rẹ ni ó fi bẹ̀rù Jèhófà.+ Àmọ́ ní báyìí, ẹni tí a jẹ ní gbèsè ti wá láti kó àwọn ọmọ mi méjèèjì kó lè fi wọ́n ṣe ẹrú.” 2 Èlíṣà wá béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé: “Kí ni kí n ṣe fún ọ? Sọ fún mi, kí lo ní sílé?” Ó fèsì pé: “Ìránṣẹ́ rẹ ò ní nǹkan kan nílé àfi ìṣà* òróró kan.”+ 3 Ó wá sọ pé: “Jáde, lọ gba àwọn òfìfo ohun èlò* lọ́wọ́ gbogbo àwọn aládùúgbò rẹ. Jẹ́ kí wọ́n pọ̀. 4 Lẹ́yìn náà kí o wọlé, kí o sì ti ilẹ̀kùn mọ́ ara rẹ àti àwọn ọmọ rẹ. Rọ òróró sínú àwọn ohun èlò náà, kí o sì gbé àwọn tó ti kún sẹ́gbẹ̀ẹ́ kan.” 5 Torí náà, ó kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀.
Nígbà tó ti ilẹ̀kùn mọ́ ara rẹ̀ àti àwọn ọmọ rẹ̀, wọ́n ń kó àwọn ohun èlò náà wá fún un, ó sì ń rọ ọ́ sínú wọn.+ 6 Nígbà tí àwọn ohun èlò náà kún, ó sọ fún ọ̀kan lára àwọn ọmọ rẹ̀ pé: “Gbé ohun èlò míì wá fún mi.”+ Àmọ́, ó sọ fún un pé: “Kò sí ohun èlò míì mọ́.” Bí òróró náà ṣe dá nìyẹn.+ 7 Nítorí náà, ó wọlé, ó sì sọ fún èèyàn Ọlọ́run tòótọ́ náà. Èlíṣà wá sọ pé: “Lọ ta òróró náà, kí o fi san gbèsè rẹ, kí ìwọ àti àwọn ọmọ rẹ sì máa fi ohun tó kù tọ́jú ara yín.”
8 Lọ́jọ́ kan, Èlíṣà lọ sí Ṣúnémù,+ níbi tí gbajúmọ̀ obìnrin kan wà, obìnrin náà sì rọ̀ ọ́ pé kó jẹun níbẹ̀.+ Nígbàkigbà tó bá kọjá, ó máa ń dúró jẹun níbẹ̀. 9 Obìnrin náà wá sọ fún ọkọ rẹ̀ pé: “Mo mọ̀ pé èèyàn mímọ́ Ọlọ́run ni ọkùnrin tó máa ń gba ibí kọjá déédéé. 10 Jọ̀ọ́, jẹ́ kí a ṣe yàrá kékeré kan sórí òrùlé,+ kí a sì gbé ibùsùn, tábìlì, àga àti ọ̀pá fìtílà kan síbẹ̀ fún un. Nígbàkigbà tó bá wá sọ́dọ̀ wa, á lè dúró síbẹ̀.”+
11 Lọ́jọ́ kan, ó wá síbẹ̀, ó sì lọ sínú yàrá tó wà lórí òrùlé láti sùn. 12 Ó wá sọ fún Géhásì,+ ìránṣẹ́ rẹ̀ pé: “Pe obìnrin ará Ṣúnémù+ yìí wá.” Torí náà, ó pè é, obìnrin náà sì dúró níwájú rẹ̀. 13 Lẹ́yìn náà, ó sọ fún Géhásì pé: “Jọ̀ọ́, sọ fún un pé, ‘O ti ṣe wàhálà gan-an nítorí wa.+ Kí ni kí n ṣe fún ọ?+ Ṣé ohun kan wà tí o fẹ́ kí n bá ọ sọ fún ọba+ tàbí fún olórí àwọn ọmọ ogun?’” Àmọ́, obìnrin náà fèsì pé: “Àárín àwọn èèyàn mi ni mò ń gbé.” 14 Torí náà, Èlíṣà sọ pé: “Kí wá ni a lè ṣe fún un?” Géhásì bá sọ pé: “Mo rí i pé kò ní ọmọ kankan,+ ọkọ rẹ̀ sì ti darúgbó.” 15 Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, ó sọ pé: “Pè é wá.” Torí náà, ó pè é, obìnrin náà sì dúró lẹ́nu ọ̀nà. 16 Ó wá sọ pé: “Ní ìwòyí ọdún tó ń bọ̀, wàá fi ọwọ́ rẹ gbé ọmọkùnrin.”+ Àmọ́, obìnrin náà sọ pé: “Rárá, ọ̀gá mi, èèyàn Ọlọ́run tòótọ́! Má parọ́ fún ìránṣẹ́ rẹ.”
17 Ṣùgbọ́n, obìnrin náà lóyún, ó sì bí ọmọkùnrin kan ní àkókò kan náà ní ọdún tó tẹ̀ lé e, gẹ́gẹ́ bí Èlíṣà ṣe sọ fún un. 18 Ọmọ náà ń dàgbà, lọ́jọ́ kan, ó jáde lọ bá bàbá rẹ̀ lọ́dọ̀ àwọn olùkórè. 19 Ó ṣáà ń sọ fún bàbá rẹ̀ pé: “Orí mi o, orí mi o!” Lẹ́yìn náà, bàbá rẹ̀ sọ fún ìránṣẹ́ rẹ̀ pé: “Gbé e lọ fún ìyá rẹ̀.” 20 Torí náà, ó gbé e lọ fún ìyá rẹ̀, ọmọ náà jókòó sórí ẹsẹ̀ ìyá rẹ̀ títí di ọ̀sán, lẹ́yìn náà ó kú.+ 21 Ni obìnrin náà bá gbé e lọ sókè, ó tẹ́ ẹ sórí ibùsùn èèyàn Ọlọ́run tòótọ́,+ ó ti ilẹ̀kùn mọ́ ọn, ó sì jáde lọ. 22 Ó wá ránṣẹ́ sí ọkọ rẹ̀ pé: “Jọ̀ọ́, fi ìránṣẹ́ kan àti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ kan ránṣẹ́ sí mi, kí n lè sáré dé ọ̀dọ̀ èèyàn Ọlọ́run tòótọ́ kí n sì pa dà.” 23 Ṣùgbọ́n ọkọ rẹ̀ sọ pé: “Kí lo fẹ́ lọ rí i fún lónìí? Òní kọ́ ni òṣùpá tuntun+ tàbí sábáàtì.” Síbẹ̀, ó sọ pé: “Kò séwu.” 24 Nítorí náà, ó di ohun tí wọ́n fi ń jókòó mọ́ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́,* ó sì sọ fún ìránṣẹ́ rẹ̀ pé: “Ó yá, gbéra. Má ṣe tẹ̀ ẹ́ jẹ́ẹ́jẹ́ẹ́ nítorí mi àfi tí mo bá ní kí o ṣe bẹ́ẹ̀.”
25 Torí náà, ó lọ sọ́dọ̀ èèyàn Ọlọ́run tòótọ́ ní Òkè Kámẹ́lì. Bí èèyàn Ọlọ́run tòótọ́ ṣe rí i lọ́ọ̀ọ́kán, ó sọ fún Géhásì, ìránṣẹ́ rẹ̀ pé: “Wò ó! Obìnrin ará Ṣúnémù yẹn ló ń bọ̀ yìí. 26 Jọ̀ọ́, sáré pàdé rẹ̀, kí o sì béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé, ‘Ṣé àlàáfíà ni? Ṣé àlàáfíà ni ọkọ rẹ wà? Ṣé àlàáfíà ni ọmọ rẹ wà?’” Ó fèsì pé: “Àlàáfíà ni.” 27 Nígbà tó dé ọ̀dọ̀ èèyàn Ọlọ́run tòótọ́ ní òkè náà, ní kíá, ó di ẹsẹ̀ rẹ̀ mú.+ Ni Géhásì bá sún mọ́ ọn láti tì í kúrò, àmọ́ èèyàn Ọlọ́run tòótọ́ sọ pé: “Fi sílẹ̀, ẹ̀dùn ọkàn ló bá a,* Jèhófà ò sì jẹ́ kí n mọ̀, bẹ́ẹ̀ ni kò sọ fún mi.” 28 Obìnrin náà wá sọ pé: “Ṣé mo ní kí olúwa mi fún mi lọ́mọ ni? Ṣé mi ò sọ pé, ‘Kí o má ṣe fún mi ní ìrètí asán’?”+
29 Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, ó sọ fún Géhásì pé: “Ká aṣọ rẹ mọ́ra,+ kí o mú ọ̀pá mi dání, kí o sì lọ. Tí o bá pàdé èèyàn, má kí i; tí ẹnikẹ́ni bá sì kí ọ, má ṣe dá a lóhùn. Kí o lọ gbé ọ̀pá mi lé ojú ọmọ náà.” 30 Ni ìyá ọmọ náà bá sọ pé: “Bí Jèhófà ti wà láàyè, tí ìwọ náà* sì wà láàyè, mi ò ní fi ọ́ sílẹ̀.”+ Torí náà, ó dìde, ó sì bá a lọ. 31 Géhásì lọ ṣáájú wọn, ó gbé ọ̀pá náà lé ojú ọmọ náà, àmọ́ kò fọhùn, kò sì mira.+ Ó pa dà lọ bá Èlíṣà, ó sì sọ fún un pé: “Ọmọ náà ò jí o.”
32 Nígbà tí Èlíṣà wọnú ilé náà, òkú ọmọ náà wà lórí ibùsùn rẹ̀.+ 33 Lẹ́yìn tó wọlé, ó ti ilẹ̀kùn, àwọn méjèèjì sì wà nínú ilé, ó wá bẹ̀rẹ̀ sí í gbàdúrà sí Jèhófà.+ 34 Ó gorí ibùsùn, ó nà lé ọmọ náà, ó sì gbé ẹnu rẹ̀ lé ẹnu ọmọ náà àti ojú rẹ̀ lé ojú ọmọ náà, ó tún gbé àtẹ́lẹwọ́ rẹ̀ lé àtẹ́lẹwọ́ ọmọ náà, ó sì nà lé e lórí síbẹ̀, ara ọmọ náà wá bẹ̀rẹ̀ sí í móoru.+ 35 Ó lọ síwájú, ó lọ sẹ́yìn nínú ilé náà, ó gorí ibùsùn náà, ó sì nà lé e lórí lẹ́ẹ̀kan sí i. Ọmọ náà bá sín nígbà méje, lẹ́yìn náà ó lajú.+ 36 Èlíṣà wá pe Géhásì, ó sì sọ pé: “Pe obìnrin ará Ṣúnémù náà wá.” Torí náà, ó pè é, ó sì wọlé wá bá a. Lẹ́yìn náà, ó sọ pé: “Gbé ọmọ rẹ.”+ 37 Lẹ́yìn tí obìnrin náà wọlé, ó kúnlẹ̀ níbi ẹsẹ̀ rẹ̀, ó tẹrí ba mọ́lẹ̀ níwájú rẹ̀, ó gbé ọmọ rẹ̀, ó sì jáde lọ.
38 Nígbà tí Èlíṣà pa dà sí Gílígálì, ìyàn mú ní ilẹ̀ náà.+ Àwọn ọmọ wòlíì+ jókòó níwájú rẹ̀, ó sì sọ fún ìránṣẹ́ rẹ̀ pé:+ “Gbé ìkòkò ńlá kaná, kí o sì se ọbẹ̀ fún àwọn ọmọ wòlíì.” 39 Ni ọ̀kan lára wọn bá jáde lọ sínú oko láti já ewéko málò, ó rí àjàrà inú igbó, ó sì ká tàgíìrì lórí rẹ̀, ó wá kó o sínú aṣọ rẹ̀. Lẹ́yìn náà, ó pa dà sílé, ó sì rẹ́ wọn sínú ìkòkò ọbẹ̀ náà, láìmọ ohun tó jẹ́. 40 Lẹ́yìn náà, wọ́n bù ú fún àwọn ọkùnrin náà láti jẹ, àmọ́ bí wọ́n ṣe fi kan ẹnu báyìí, wọ́n figbe ta pé: “Èèyàn Ọlọ́run tòótọ́, ikú wà nínú ìkòkò náà.” Wọn ò sì lè jẹ ẹ́. 41 Torí náà, ó sọ pé: “Ẹ bu ìyẹ̀fun wá.” Lẹ́yìn tó bù ú sínú ìkòkò náà, ó sọ pé: “Ẹ bù ú fún àwọn èèyàn náà.” Kò sì sí ohun eléwu nínú ìkòkò náà mọ́.+
42 Ọkùnrin kan wá láti Baali-ṣálíṣà,+ ó sì kó ogún (20) búrẹ́dì ọkà bálì+ tí wọ́n fi àkọ́so èso ṣe àti àpò ọkà+ tuntun wá. Ìgbà náà ni Èlíṣà sọ pé: “Kó wọn fún àwọn èèyàn náà kí wọ́n lè jẹun.” 43 Síbẹ̀, ìránṣẹ́ rẹ̀ sọ pé: “Báwo ni màá ṣe gbé nǹkan yìí síwájú ọgọ́rùn-ún (100) èèyàn?”+ Ó fèsì pé: “Kó wọn fún àwọn èèyàn náà kí wọ́n lè jẹun, nítorí ohun tí Jèhófà sọ nìyí, ‘Wọ́n á jẹ, á sì tún ṣẹ́ kù.’”+ 44 Ni ó bá gbé e síwájú wọn, wọ́n jẹ, ó sì tún ṣẹ́ kù+ gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ Jèhófà.
5 Ọkùnrin olókìkí kan wà tó ń jẹ́ Náámánì, òun ni olórí ọmọ ogun ọba Síríà, ẹni ńlá ni lójú olúwa rẹ̀ nítorí pé ipasẹ̀ rẹ̀ ni Jèhófà fi mú kí Síríà ṣẹ́gun.* Jagunjagun tó lákíkanjú ni, bó tilẹ̀ jẹ́ pé adẹ́tẹ̀ ni.* 2 Ìgbà kan wà tí àwọn ará Síríà lọ kó ohun ìní àwọn èèyàn, wọ́n mú ọmọbìnrin kékeré kan lẹ́rú láti ilẹ̀ Ísírẹ́lì, ó sì di ìránṣẹ́ ìyàwó Náámánì. 3 Ó sọ fún ọ̀gá rẹ̀ obìnrin pé: “Ká ní olúwa mi lè lọ rí wòlíì+ tó wà ní Samáríà ni! Ó máa wo ẹ̀tẹ̀ rẹ̀ sàn.”+ 4 Torí náà, ó* lọ fi ohun tí ọmọbìnrin ará Ísírẹ́lì náà sọ tó olúwa rẹ̀ létí.
5 Nígbà náà, ọba Síríà sọ pé: “Ó yá, gbéra! Màá fi lẹ́tà kan rán ọ sí ọba Ísírẹ́lì.” Nítorí náà, ó lọ, ó kó tálẹ́ńtì* fàdákà mẹ́wàá àti ẹgbẹ̀rún mẹ́fà (6,000) ẹyọ wúrà àti ìpààrọ̀ aṣọ mẹ́wàá dání. 6 Ó mú lẹ́tà náà wá fún ọba Ísírẹ́lì, lẹ́tà náà kà báyìí pé: “Mo rán ìránṣẹ́ mi Náámánì sí ọ pẹ̀lú lẹ́tà yìí, kí o lè wo ẹ̀tẹ̀ rẹ̀ sàn.” 7 Gbàrà tí ọba Ísírẹ́lì ka lẹ́tà náà, ó fa aṣọ rẹ̀ ya, ó sì sọ pé: “Ṣé Ọlọ́run ni mí, tí màá lè pani, tí màá sì lè dáni sí?+ Nítorí ọba Síríà rán ọkùnrin yìí sí mi pé kí n wo ẹ̀tẹ̀ rẹ̀ sàn! Àbí ẹ̀yin náà ò rí i pé wàhálà ló ń wá.”
8 Àmọ́ nígbà tí Èlíṣà, èèyàn Ọlọ́run tòótọ́ gbọ́ pé ọba Ísírẹ́lì ti fa aṣọ rẹ̀ ya, ní kíá, ó ránṣẹ́ sí ọba pé: “Kí ló dé tí o fi fa aṣọ rẹ ya? Jọ̀ọ́, jẹ́ kó wá sọ́dọ̀ mi, kó lè mọ̀ pé wòlíì kan wà ní Ísírẹ́lì.”+ 9 Nítorí náà, Náámánì wá, tòun ti àwọn ẹṣin àti àwọn kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀, ó sì dúró lẹ́nu ọ̀nà ilé Èlíṣà. 10 Àmọ́, Èlíṣà ní kí ìránṣẹ́ kan lọ sọ fún un pé: “Lọ wẹ̀ nígbà méje+ ní odò Jọ́dánì,+ ara rẹ á pa dà sí bó ṣe wà tẹ́lẹ̀, wàá sì mọ́.” 11 Náámánì bá bínú, ó sì yíjú pa dà, ó ní: “Ohun tí mo rò ni pé, ‘Á jáde wá bá mi, á dúró níbí yìí, á sì pe orúkọ Jèhófà Ọlọ́run rẹ̀ bó ṣe ń gbé ọwọ́ rẹ̀ síwá-sẹ́yìn lórí ẹ̀tẹ̀ náà láti wò ó sàn.’ 12 Ṣé Ábánà àti Fápárì, àwọn odò Damásíkù,+ kò dára ju gbogbo omi Ísírẹ́lì ni? Ṣé mi ò lè wẹ̀ nínú wọn kí n sì mọ́ ni?” Bó ṣe yíjú pa dà nìyẹn, ó sì ń bínú lọ.
13 Àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ wá bá a, wọ́n sì sọ pé: “Bàbá mi, ká ní ohun ńlá kan ni wòlíì náà sọ fún ọ pé kí o ṣe, ṣé o ò ní ṣe é ni? Ká má ṣẹ̀ṣẹ̀ wá sọ ti ohun kékeré tó sọ fún ọ yìí pé, ‘Wẹ̀, kí o sì mọ́’?” 14 Ni ó bá lọ síbẹ̀, ó sì ri* ara rẹ̀ bọ inú odò Jọ́dánì ní ìgbà méje gẹ́gẹ́ bí èèyàn Ọlọ́run tòótọ́ ti sọ.+ Lẹ́yìn náà, ara rẹ̀ pa dà sí bó ṣe wà tẹ́lẹ̀, ó rí bí ara ọmọ kékeré,+ ó sì mọ́.+
15 Lẹ́yìn náà, ó pa dà lọ sọ́dọ̀ èèyàn Ọlọ́run tòótọ́,+ òun pẹ̀lú gbogbo àwọn tó tẹ̀ lé e,* ó dúró níwájú rẹ̀, ó sì sọ pé: “Mo ti wá mọ̀ báyìí pé kò sí Ọlọ́run níbikíbi láyé, àfi ní Ísírẹ́lì.+ Jọ̀ọ́, gba ẹ̀bùn* yìí lọ́wọ́ ìránṣẹ́ rẹ.” 16 Àmọ́ Èlíṣà sọ pé: “Bí Jèhófà tí mò ń sìn* ti wà láàyè, mi ò ní gbà á.”+ Ó ń rọ̀ ọ́ pé kó gbà á, ṣùgbọ́n ó kọ̀ ọ́. 17 Níkẹyìn, Náámánì sọ pé: “Tí o kò bá gbà á, jọ̀ọ́, jẹ́ kí wọ́n bu erùpẹ̀ ilẹ̀ yìí tí ó tó ẹrù kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́* méjì fún ìránṣẹ́ rẹ, torí ìránṣẹ́ rẹ kò ní rú ẹbọ sísun tàbí ẹbọ sí ọlọ́run kankan mọ́, àfi Jèhófà. 18 Àmọ́, kí Jèhófà dárí ji ìránṣẹ́ rẹ nínú ohun kan ṣoṣo yìí: Nígbà tí olúwa mi bá lọ sí ilé* Rímónì láti forí balẹ̀ níbẹ̀, ó máa ń fara tì mí, torí náà mo ní láti forí balẹ̀ ní ilé Rímónì. Kí Jèhófà jọ̀ọ́ dárí ji ìránṣẹ́ rẹ nígbà tí mo bá forí balẹ̀ ní ilé Rímónì.” 19 Èlíṣà bá sọ fún un pé: “Máa lọ ní àlàáfíà.” Lẹ́yìn tó ti kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀, tó sì ti rìn jìnnà díẹ̀, 20 Géhásì,+ ìránṣẹ́ Èlíṣà èèyàn Ọlọ́run tòótọ́+ sọ lọ́kàn ara rẹ̀ pé: ‘Ṣé bí ọ̀gá mi á ṣe jẹ́ kí Náámánì ará Síríà+ yìí lọ láìgba ohun tó mú wá nìyẹn? Bí Jèhófà ti wà láàyè, màá sá tẹ̀ lé e, màá sì gba nǹkan kan lọ́wọ́ rẹ̀.’ 21 Torí náà, Géhásì sá tẹ̀ lé Náámánì. Nígbà tí Náámánì rí i pé ẹnì kan ń sáré tẹ̀ lé òun, ó sọ̀ kalẹ̀ lórí kẹ̀kẹ́ ẹṣin rẹ̀ láti pàdé rẹ̀, ó sì sọ pé: “Ṣé àlàáfíà ni?” 22 Ó fèsì pé: “Àlàáfíà ni. Ọ̀gá mi ló rán mi, ó ní, ‘Wò ó! Àwọn ọ̀dọ́kùnrin méjì lára àwọn ọmọ wòlíì ṣẹ̀ṣẹ̀ dé sọ́dọ̀ mi láti agbègbè olókè Éfúrémù. Jọ̀ọ́, fún wọn ní tálẹ́ńtì fàdákà kan àti ìpààrọ̀ aṣọ méjì.’”+ 23 Náámánì wá sọ pé: “Ó yá, kó tálẹ́ńtì méjì.” Ó ń rọ̀ ọ́,+ ó sì di tálẹ́ńtì fàdákà méjì sínú àpò méjì pẹ̀lú ìpààrọ̀ aṣọ méjì, ó gbé wọn fún méjì lára àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀, wọ́n sì ń gbé e lọ níwájú rẹ̀.
24 Nígbà tó dé Ófélì,* ó gbà á lọ́wọ́ wọn, ó kó wọn sínú ilé, ó sì ní kí àwọn ọkùnrin náà máa lọ. Lẹ́yìn tí wọ́n ti lọ, 25 ó wọlé, ó sì dúró lẹ́gbẹ̀ẹ́ ọ̀gá rẹ̀. Èlíṣà wá béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé: “Ibo lo ti ń bọ̀, Géhásì?” Àmọ́, ó dáhùn pé: “Ìránṣẹ́ rẹ ò lọ síbì kankan.”+ 26 Èlíṣà bá sọ fún un pé: “Ṣé o rò pé mi ò máa fọkàn bá ọ lọ nígbà tí ọkùnrin náà sọ̀ kalẹ̀ lórí kẹ̀kẹ́ ẹṣin rẹ̀ láti pàdé rẹ? Ṣé àkókò yìí ló yẹ kéèyàn gba fàdákà tàbí àwọn aṣọ tàbí àwọn oko ólífì tàbí àwọn ọgbà àjàrà tàbí àgùntàn tàbí màlúù tàbí àwọn ìránṣẹ́ lọ́kùnrin àti lóbìnrin?+ 27 Ní báyìí, ẹ̀tẹ̀ Náámánì+ yóò lẹ̀ mọ́ ìwọ àti àtọmọdọ́mọ rẹ títí láé.” Lójú ẹsẹ̀, ó di adẹ́tẹ̀, ẹ̀tẹ̀ rẹ̀ funfun bíi yìnyín,+ ó sì jáde kúrò níwájú rẹ̀.
6 Àwọn ọmọ wòlíì+ sọ fún Èlíṣà pé: “Wò ó! Ibi tí à ń gbé lọ́dọ̀ rẹ ti há jù fún wa. 2 Jọ̀ọ́, jẹ́ kí a lọ sí Jọ́dánì. Kí ẹnì kọ̀ọ̀kan wa gbé ìtì igi kan níbẹ̀, kí a sì ṣe ibì kan síbẹ̀ tí a lè máa gbé.” Ó sọ pé: “Ẹ lọ.” 3 Ọ̀kan lára wọn sọ pé: “Jọ̀ọ́, ṣé wàá bá àwọn ìránṣẹ́ rẹ lọ?” Ó fèsì pé: “Màá lọ.” 4 Torí náà, ó bá wọn lọ, nígbà tí wọ́n dé Jọ́dánì, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í gé igi. 5 Bí ọ̀kan lára wọn ṣe ń gé igi lọ́wọ́, irin àáké rẹ̀ já bọ́ sínú omi, ó sì kígbe pé: “Áà, ọ̀gá mi, ńṣe la yá a!” 6 Èèyàn Ọlọ́run tòótọ́ wá bi í pé: “Ibo ló bọ́ sí?” Torí náà, ó fi ibẹ̀ hàn án. Ó wá gé igi kan, ó sọ ọ́ sí ibẹ̀, ó sì mú kí irin àáké náà léfòó. 7 Ó sọ pé: “Mú un jáde.” Torí náà, ó na ọwọ́ rẹ̀, ó sì mú un.
8 Nígbà náà, ọba Síríà jáde lọ láti bá Ísírẹ́lì jà.+ Ó fọ̀rọ̀ lọ àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀, ó sì sọ pé: “Ibi báyìí-báyìí ni a máa dó sí.” 9 Lẹ́yìn náà, èèyàn Ọlọ́run tòótọ́+ ránṣẹ́ sí ọba Ísírẹ́lì pé: “Ṣọ́ra, má ṣe gba ibí kọjá, torí pé àwọn ará Síríà ń bọ̀ wá síbẹ̀.” 10 Nítorí náà, ọba Ísírẹ́lì ránṣẹ́ láti kìlọ̀ fún àwọn tó wà ní ibi tí èèyàn Ọlọ́run tòótọ́ sọ fún un nípa rẹ̀. Èlíṣà ò yéé kìlọ̀ fún un, ọ̀pọ̀ ìgbà* ni ọba Ísírẹ́lì sì yẹra fún ibẹ̀.+
11 Èyí bí ọba Síríà nínú,* torí náà ó pe àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀, ó sì sọ fún wọn pé: “Ẹ sọ fún mi! Ta ló ń gbè sẹ́yìn ọba Ísírẹ́lì lára wa?” 12 Ìgbà náà ni ọ̀kan lára àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ sọ pé: “Kì í ṣe ìkankan lára wa, olúwa mi ọba! Èlíṣà, wòlíì tó wà ní Ísírẹ́lì lẹni tó ń sọ àwọn ohun tí o bá sọ nínú yàrá rẹ fún ọba Ísírẹ́lì.”+ 13 Ọba wá sọ pé: “Ẹ lọ wá ibi tó wà, kí n lè rán àwọn èèyàn lọ mú un.” Nígbà tó yá, wọ́n ròyìn fún un pé: “Ó wà ní Dótánì.”+ 14 Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, ó rán àwọn ẹṣin àti àwọn kẹ̀kẹ́ ogun pẹ̀lú ọ̀pọ̀ ọmọ ogun lọ síbẹ̀; wọ́n lọ síbẹ̀ ní òru, wọ́n sì yí ìlú náà ká.
15 Nígbà tí ìránṣẹ́* èèyàn Ọlọ́run tòótọ́ dìde ní àárọ̀ kùtù, tí ó sì jáde, ó rí i tí àwọn ọmọ ogun pẹ̀lú àwọn ẹṣin àti àwọn kẹ̀kẹ́ ogun yí ìlú náà ká. Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, ìránṣẹ́ náà sọ fún un pé: “Áà, ọ̀gá mi! Kí la máa ṣe?” 16 Ṣùgbọ́n ó sọ pé: “Má bẹ̀rù!+ Torí pé àwọn tó wà pẹ̀lú wa pọ̀ ju àwọn tó wà pẹ̀lú wọn.”+ 17 Èlíṣà wá bẹ̀rẹ̀ sí í gbàdúrà, ó sọ pé: “Jèhófà, jọ̀ọ́, la ojú rẹ̀, kó lè ríran.”+ Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, Jèhófà la ojú ìránṣẹ́ náà, ó sì ríran, wò ó! àwọn ẹṣin àti àwọn kẹ̀kẹ́ ogun oníná+ kún agbègbè olókè náà, wọ́n sì yí Èlíṣà ká.+
18 Nígbà tí àwọn ará Síríà náà wá bá a, Èlíṣà gbàdúrà sí Jèhófà, ó sì sọ pé: “Jọ̀ọ́, bu ìfọ́jú lu orílẹ̀-èdè yìí.”+ Nítorí náà, ó bu ìfọ́jú lù wọ́n bí Èlíṣà ṣe béèrè. 19 Èlíṣà wá sọ fún wọn pé: “Ibí kọ́ ni ọ̀nà, ibí kọ́ sì ni ìlú náà. Ẹ tẹ̀ lé mi, ẹ jẹ́ kí n mú yín lọ sọ́dọ̀ ọkùnrin tí ẹ̀ ń wá.” Àmọ́, ó mú wọn lọ sí Samáríà.+
20 Nígbà tí wọ́n dé Samáríà, Èlíṣà sọ pé: “Jèhófà, la ojú wọn kí wọ́n lè ríran.” Nítorí náà, Jèhófà la ojú wọn, wọ́n sì rí i pé àárín Samáríà ni àwọn wà. 21 Nígbà tí ọba Ísírẹ́lì rí wọn, ó sọ fún Èlíṣà pé: “Ṣé kí n pa wọ́n, ṣé kí n pa wọ́n, bàbá mi?” 22 Àmọ́, ó sọ pé: “O ò gbọ́dọ̀ pa wọ́n. Ṣé o máa ń pa àwọn tí o fi idà rẹ àti ọrun rẹ mú lẹ́rú ni? Ṣe ni kí o fún wọn ní oúnjẹ àti omi, kí wọ́n lè jẹ, kí wọ́n mu,+ kí wọ́n sì pa dà sọ́dọ̀ olúwa wọn.” 23 Torí náà, ó se àsè ńlá fún wọn, wọ́n jẹ, wọ́n sì mu, lẹ́yìn náà ó ní kí wọ́n pa dà sọ́dọ̀ olúwa wọn. Àwọn jàǹdùkú* ilẹ̀ Síríà+ kò sì tún wá sí ilẹ̀ Ísírẹ́lì mọ́.
24 Lẹ́yìn ìgbà náà, Bẹni-hádádì ọba Síríà kó gbogbo ọmọ ogun* rẹ̀ jọ, ó sì lọ dó ti Samáríà.+ 25 Torí náà, ìyàn ńlá+ kan mú ní Samáríà, wọ́n sì dó tì í títí wọ́n fi ń ta orí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́+ kan ní ọgọ́rin (80) ẹyọ fàdákà, ìlàrin òṣùwọ̀n káàbù* imí àdàbà sì di ẹyọ fàdákà márùn-ún. 26 Bí ọba Ísírẹ́lì ṣe ń kọjá lọ lórí ògiri, obìnrin kan ké sí i pé: “Olúwa mi ọba, gbà wá!” 27 Ó fèsì pé: “Bí Jèhófà ò bá gbà ọ́, báwo ni mo ṣe lè gbà ọ́? Ṣé láti ibi ìpakà ni? Àbí láti ibi tí wọ́n ti ń fún wáìnì tàbí òróró?” 28 Ọba wá béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé: “Kí ni ìṣòro rẹ?” Ó dáhùn pé: “Obìnrin yìí sọ fún mi pé, ‘Mú ọmọ rẹ wá, kí a lè jẹ ẹ́ lónìí, a ó sì jẹ ọmọ tèmi ní ọ̀la.’+ 29 Torí náà, a se ọmọ mi, a sì jẹ ẹ́.+ Lọ́jọ́ kejì, mo sọ fún un pé, ‘Mú ọmọ rẹ wá kí a lè jẹ ẹ́.’ Àmọ́, ó fi ọmọ rẹ̀ pa mọ́.”
30 Bí ọba ṣe gbọ́ ọ̀rọ̀ obìnrin náà, ó fa aṣọ rẹ̀ ya.+ Nígbà tó sì ń kọjá lọ lórí ògiri, àwọn èèyàn rí i pé ó wọ aṣọ ọ̀fọ̀* sí abẹ́ aṣọ* rẹ̀. 31 Ni ó bá sọ pé: “Kí Ọlọ́run fìyà jẹ mí gan-an, bí orí Èlíṣà ọmọ Ṣáfátì kò bá kúrò lọ́rùn rẹ̀ lónìí!”+
32 Èlíṣà jókòó nínú ilé rẹ̀, àwọn àgbààgbà sì jókòó sọ́dọ̀ rẹ̀. Ọba rán ọkùnrin kan ṣáájú ara rẹ̀, àmọ́ kí òjíṣẹ́ náà tó débẹ̀, Èlíṣà sọ fún àwọn àgbààgbà náà pé: “Ǹjẹ́ ẹ rí bí ọmọ apààyàn+ yìí ṣe ránṣẹ́ pé kí wọ́n wá bẹ́ mi lórí? Ẹ máa ṣọ́nà, tí òjíṣẹ́ náà bá dé, kí ẹ pa ilẹ̀kùn dé, kí ẹ sì di ilẹ̀kùn náà mú kó má bàa ráyè wọlé. Ǹjẹ́ kì í ṣe ìró ẹsẹ̀ olúwa rẹ̀ ló ń dún bọ̀ lẹ́yìn rẹ̀ yẹn?” 33 Bó ṣe ń bá wọn sọ̀rọ̀ lọ́wọ́, òjíṣẹ́ náà dé ọ̀dọ̀ rẹ̀, ọba sì sọ pé: “Ọ̀dọ̀ Jèhófà ni àjálù yìí ti wá. Kí nìdí tí màá tún fi dúró de Jèhófà?”
7 Nígbà náà, Èlíṣà sọ pé, “Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ Jèhófà. Ohun tí Jèhófà sọ nìyí: ‘Ní ìwòyí ọ̀la, òṣùwọ̀n síà* ìyẹ̀fun kíkúnná yóò di ṣékélì* kan, òṣùwọ̀n síà méjì ọkà bálì yóò sì di ṣékélì kan ní ẹnubodè* Samáríà.’”+ 2 Ni olùrànlọ́wọ́ ọ̀gágun, ẹni tí ọba fọkàn tán bá dá èèyàn Ọlọ́run tòótọ́ lóhùn pé: “Ká tiẹ̀ ní Jèhófà ṣí ibú omi ojú ọ̀run sílẹ̀, ṣé irú nǹkan* yìí lè ṣẹlẹ̀?”+ Èlíṣà dáhùn pé: “Wàá fi ojú ara rẹ rí i,+ ṣùgbọ́n o ò ní jẹ nínú rẹ̀.”+
3 Àwọn adẹ́tẹ̀ mẹ́rin kan wà ní ibi àtiwọ ẹnubodè ìlú,+ wọ́n sì sọ fún ara wọn pé: “Kí nìdí tí a fi máa jókòó síbí títí a ó fi kú? 4 Tí a bá ní ká wọnú ìlú nígbà tí ìyàn ṣì mú nínú ìlú,+ ibẹ̀ la máa kú sí. Tí a bá sì jókòó síbí, a ṣì máa kú. Torí náà, ẹ jẹ́ ká lọ sí ibùdó àwọn ará Síríà. Tí wọ́n bá dá ẹ̀mí wa sí, a ò ní kú, ṣùgbọ́n tí wọ́n bá pa wá, a kú náà nìyẹn.” 5 Ni wọ́n bá dìde nígbà tí ilẹ̀ ti ṣú, wọ́n sì wọ ibùdó àwọn ará Síríà. Nígbà tí wọ́n dé ẹ̀yìn ibùdó àwọn ará Síríà, kò sí ẹnì kankan níbẹ̀.
6 Jèhófà ti mú kí ibùdó àwọn ará Síríà gbọ́ ìró àwọn kẹ̀kẹ́ ogun, ìró àwọn ẹṣin àti ti ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọmọ ogun.+ Torí náà, wọ́n sọ fún ara wọn pé: “Ẹ wò ó! Ọba Ísírẹ́lì ti háyà àwọn ọba àwọn ọmọ Hétì àti àwọn ọba Íjíbítì láti wá gbéjà kò wá!” 7 Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, wọ́n dìde, wọ́n sì sá lọ nígbà tí ilẹ̀ ti ṣú, wọ́n fi àwọn àgọ́ wọn àti àwọn ẹṣin wọn àti àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ wọn sílẹ̀, gbogbo ibùdó náà wà bó ṣe wà, wọ́n sì sá lọ nítorí ẹ̀mí* wọn.
8 Nígbà tí àwọn adẹ́tẹ̀ yìí dé ẹ̀yìn ibùdó náà, wọ́n wọnú àgọ́ kan, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í jẹ, wọ́n sì ń mu. Wọ́n kó fàdákà, wúrà àti aṣọ láti ibẹ̀, wọ́n sì lọ kó wọn pa mọ́. Lẹ́yìn náà, wọ́n pa dà wá, wọ́n wọnú àgọ́ míì, wọ́n kó àwọn nǹkan láti ibẹ̀, wọ́n sì lọ kó wọn pa mọ́.
9 Níkẹyìn, wọ́n sọ fún ara wọn pé: “Ohun tí à ń ṣe yìí kò dára. Ọjọ́ ìròyìn ayọ̀ lọjọ́ òní! Tí a bá dákẹ́, tí a sì dúró títí ilẹ̀ á fi mọ́, ìyà máa tọ́ sí wa. Torí náà, ẹ jẹ́ ká lọ ròyìn nǹkan yìí ní ilé ọba.” 10 Nítorí náà, wọ́n lọ, wọ́n pe àwọn aṣọ́bodè ìlú náà, wọ́n sì ròyìn fún wọn pé: “A wọnú ibùdó àwọn ará Síríà, àmọ́ kò sí ẹnì kankan níbẹ̀, a ò gbọ́ ìró èèyàn kankan. Àwọn ẹṣin àti àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ tí wọ́n dè mọ́lẹ̀ àti àwọn àgọ́ tó wà bí wọ́n ṣe wà nìkan la rí.” 11 Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, àwọn aṣọ́bodè lọ ròyìn fún àwọn tó wà ní ilé ọba.
12 Ní kíá, ọba dìde lóru, ó sì sọ fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pé: “Ẹ jọ̀ọ́, ẹ jẹ́ kí n sọ ohun tí àwọn ará Síríà fẹ́ ṣe sí wa fún yín. Wọ́n mọ̀ pé ebi ń pa wá,+ torí bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ṣe kúrò ní ibùdó láti lọ fara pa mọ́ ní pápá, wọ́n sọ pé, ‘Wọ́n máa jáde kúrò nínú ìlú, a ó mú wọn láàyè, a ó sì wọnú ìlú náà.’”+ 13 Ni ọ̀kan lára àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ bá sọ pé: “Jọ̀ọ́, jẹ́ kí àwọn ọkùnrin kan mú márùn-ún lára àwọn ẹṣin tó ṣẹ́ kù nínú ìlú. Wò ó! Ohun tó máa ṣẹlẹ̀ sí gbogbo àwọn èèyàn Ísírẹ́lì tó ṣẹ́ kù síbí náà ló máa ṣẹlẹ̀ sí wọn. Àbí kó jẹ́ pé, ohun tó ṣẹlẹ̀ sí àwọn èèyàn Ísírẹ́lì tó ti kú náà ló máa ṣẹlẹ̀ sí wọn. Torí náà, jẹ́ ká rán wọn, ká sì wo ohun tó máa ṣẹlẹ̀.” 14 Torí náà, wọ́n mú kẹ̀kẹ́ ẹṣin méjì pẹ̀lú àwọn ẹṣin, ọba sì rán wọn lọ sí ibùdó àwọn ará Síríà, ó sọ pé: “Ẹ lọ wò ó.” 15 Wọ́n tẹ̀ lé wọn títí dé Jọ́dánì, àwọn ẹ̀wù àti àwọn nǹkan èlò tí àwọn ará Síríà jù dà nù bí wọ́n ṣe ń sá lọ kíjokíjo kún gbogbo ojú ọ̀nà. Àwọn òjíṣẹ́ náà pa dà, wọ́n sì ròyìn fún ọba.
16 Àwọn èèyàn náà bá jáde lọ, wọ́n sì kó àwọn nǹkan tó wà ní ibùdó àwọn ará Síríà, tó fi jẹ́ pé òṣùwọ̀n síà ìyẹ̀fun kíkúnná di ṣékélì kan, òṣùwọ̀n síà méjì ọkà bálì sì di ṣékélì kan, gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ Jèhófà.+ 17 Ọba ti yan olùrànlọ́wọ́ ọ̀gágun, ẹni tó fọkàn tán, láti máa bójú tó ẹnubodè, àmọ́ àwọn èèyàn náà tẹ̀ ẹ́ pa ní ẹnubodè, bí èèyàn Ọlọ́run tòótọ́ ṣe sọ fún ọba nígbà tó wá sọ́dọ̀ rẹ̀. 18 Ọ̀rọ̀ náà ṣẹ gẹ́lẹ́ bí èèyàn Ọlọ́run tòótọ́ ṣe sọ fún ọba pé: “Ní ìwòyí ọ̀la, òṣùwọ̀n síà méjì ọkà bálì yóò di ṣékélì kan, òṣùwọ̀n síà ìyẹ̀fun kíkúnná yóò sì di ṣékélì kan ní ẹnubodè Samáríà.”+ 19 Àmọ́ ohun tí olùrànlọ́wọ́ ọ̀gágun sọ fún èèyàn Ọlọ́run tòótọ́ ni pé: “Ká tiẹ̀ ní Jèhófà ṣí ibú omi ojú ọ̀run sílẹ̀, ṣé irú nǹkan* yìí lè ṣẹlẹ̀?” Èlíṣà sì fún un lésì pé: “Wàá fi ojú ara rẹ rí i, ṣùgbọ́n o ò ní jẹ nínú rẹ̀.” 20 Ohun tó sì ṣẹlẹ̀ sí i gan-an nìyẹn, torí pé àwọn èèyàn náà tẹ̀ ẹ́ pa ní ẹnubodè.
8 Èlíṣà sọ fún ìyá ọmọ tí ó jí dìde* pé:+ “Gbéra, ìwọ àti agbo ilé rẹ, kí o lọ máa gbé ní ilẹ̀ èyíkéyìí tí o bá rí, kí o sì di àjèjì níbẹ̀, nítorí Jèhófà ti kéde ìyàn,+ ọdún méje ni ìyàn yóò sì fi mú ní ilẹ̀ yìí.” 2 Nítorí náà, obìnrin náà dìde, ó sì ṣe ohun tí èèyàn Ọlọ́run tòótọ́ sọ. Òun àti agbo ilé rẹ̀ jáde lọ, wọ́n sì lọ ń gbé ní ilẹ̀ àwọn Filísínì+ fún ọdún méje.
3 Nígbà tí ọdún méje parí, obìnrin náà pa dà láti ilẹ̀ àwọn Filísínì, ó sì lọ bẹ ọba nítorí ilé rẹ̀ àti ilẹ̀ rẹ̀. 4 Nígbà náà, ọba ń bá Géhásì ìránṣẹ́ èèyàn Ọlọ́run tòótọ́ sọ̀rọ̀ lọ́wọ́, ó ní: “Jọ̀wọ́, ròyìn fún mi nípa gbogbo ohun ńlá tí Èlíṣà ti ṣe.”+ 5 Bó ṣe ń ròyìn fún ọba nípa bó ṣe jí ẹni tó kú dìde,+ obìnrin tí Èlíṣà jí ọmọ rẹ̀ dìde wá sọ́dọ̀ ọba, ó wá bẹ̀ ẹ́ nítorí ilé rẹ̀ àti ilẹ̀ rẹ̀.+ Lójú ẹsẹ̀, Géhásì sọ pé: “Olúwa mi ọba, obìnrin náà nìyí, ọmọ rẹ̀ tí Èlíṣà jí dìde sì nìyí.” 6 Ni ọba bá béèrè lọ́wọ́ obìnrin náà, ó sì ròyìn ohun tó ṣẹlẹ̀ fún ọba. Lẹ́yìn náà, ọba yan òṣìṣẹ́ ààfin kan fún un, ó sì sọ fún òṣìṣẹ́ náà pé: “Gbogbo ohun tó jẹ́ tirẹ̀ àti gbogbo ohun tí oko rẹ̀ mú jáde láti ọjọ́ tó ti kúrò ní ilẹ̀ yìí títí di báyìí ni kí o dá pa dà fún un.”
7 Èlíṣà wá sí Damásíkù+ nígbà tí Bẹni-hádádì+ ọba Síríà ń ṣàìsàn. Torí náà, wọ́n ròyìn fún ọba pé: “Èèyàn Ọlọ́run tòótọ́+ ti dé síbí o.” 8 Ọba wá sọ fún Hásáẹ́lì pé:+ “Mú ẹ̀bùn dání, kí o sì lọ bá èèyàn Ọlọ́run tòótọ́.+ Ní kí ó bá mi wádìí lọ́dọ̀ Jèhófà pé, ‘Ṣé màá bọ́ lọ́wọ́ àìsàn yìí?’” 9 Hásáẹ́lì lọ bá a, pẹ̀lú ẹ̀bùn lọ́wọ́, gbogbo oríṣiríṣi ohun rere tó wà ní Damásíkù, ogójì (40) ẹrù ràkúnmí. Ó wá dúró níwájú rẹ̀, ó sì sọ pé: “Ọmọ rẹ, Bẹni-hádádì ọba Síríà, rán mi sí ọ láti béèrè lọ́wọ́ rẹ pé, ‘Ṣé màá bọ́ lọ́wọ́ àìsàn yìí?’” 10 Èlíṣà dá a lóhùn pé: “Lọ sọ fún un pé, ‘Ó dájú pé ara rẹ máa yá,’ àmọ́ Jèhófà ti fi hàn mí pé ó dájú pé ó máa kú.”+ 11 Ó wá tẹjú mọ́ Hásáẹ́lì títí ojú fi ń tì í. Lẹ́yìn náà, èèyàn Ọlọ́run tòótọ́ bú sẹ́kún. 12 Hásáẹ́lì béèrè pé: “Kí ló dé tí olúwa mi fi ń sunkún?” Ó fèsì pé: “Nítorí mo mọ jàǹbá tí o máa ṣe fún àwọn èèyàn Ísírẹ́lì.+ Wàá sọ iná sí àwọn ibi olódi wọn, wàá fi idà pa àwọn ààyò ọkùnrin wọn, wàá fọ́ àwọn ọmọ wọn mọ́lẹ̀, wàá sì la inú àwọn aboyún wọn.”+ 13 Hásáẹ́lì sọ pé: “Báwo ni èmi ìránṣẹ́ rẹ, tí mo jẹ́ ajá lásán-làsàn, ṣe lè ṣe irú nǹkan yìí?” Àmọ́ Èlíṣà sọ pé: “Jèhófà ti fi hàn mí pé wàá di ọba lórí Síríà.”+
14 Lẹ́yìn náà, ó kúrò lọ́dọ̀ Èlíṣà, ó sì pa dà sọ́dọ̀ olúwa rẹ̀, olúwa rẹ̀ béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé: “Kí ni Èlíṣà sọ fún ọ?” Ó fèsì pé: “Ó sọ fún mi pé dájúdájú ara rẹ máa yá.”+ 15 Àmọ́ lọ́jọ́ kejì, Hásáẹ́lì mú aṣọ tí wọ́n ń dà bo ibùsùn, ó tẹ̀ ẹ́ bọ omi, ó sì fi bo ojú olúwa rẹ̀ mọ́lẹ̀* títí ó fi kú.+ Hásáẹ́lì sì di ọba ní ipò rẹ̀.+
16 Ní ọdún karùn-ún Jèhórámù+ ọmọ Áhábù ọba Ísírẹ́lì, nígbà tí Jèhóṣáfátì ṣì jẹ́ ọba Júdà, Jèhórámù+ ọmọ Jèhóṣáfátì ọba Júdà, di ọba. 17 Ẹni ọdún méjìlélọ́gbọ̀n (32) ni nígbà tó jọba, ọdún mẹ́jọ ló sì fi ṣàkóso ní Jerúsálẹ́mù. 18 Ó rìn ní ọ̀nà àwọn ọba Ísírẹ́lì,+ bí àwọn ọba tó wá láti ilé Áhábù ti ṣe,+ nítorí ọmọ Áhábù ló fi ṣe aya;+ ó sì ń ṣe ohun tó burú ní ojú Jèhófà.+ 19 Àmọ́ Jèhófà ò fẹ́ pa Júdà run nítorí Dáfídì ìránṣẹ́ rẹ̀,+ torí pé ó ti ṣèlérí fún Dáfídì pé òun àti àwọn ọmọ rẹ̀ lá máa ṣàkóso*+ títí lọ.
20 Nígbà ayé rẹ̀, Édómù ṣọ̀tẹ̀ sí Júdà,+ wọ́n sì fi ọba jẹ lórí ara wọn.+ 21 Nítorí náà, Jèhórámù sọdá lọ sọ́dọ̀ Sáírì pẹ̀lú gbogbo kẹ̀kẹ́ ẹṣin rẹ̀, ó dìde ní òru, ó sì ṣẹ́gun àwọn ọmọ Édómù tí wọ́n yí i ká àti àwọn olórí kẹ̀kẹ́ ẹṣin; àwọn ọmọ ogun náà sì sá lọ sínú àgọ́ wọn. 22 Àmọ́ Édómù ṣì ń ṣọ̀tẹ̀ sí Júdà títí di òní yìí. Líbínà+ pẹ̀lú ṣọ̀tẹ̀ ní àkókò yẹn.
23 Ní ti ìyókù ìtàn Jèhórámù àti gbogbo ohun tí ó ṣe, ǹjẹ́ kò wà lákọsílẹ̀ nínú ìwé ìtàn ìgbà àwọn ọba Júdà? 24 Níkẹyìn, Jèhórámù sinmi pẹ̀lú àwọn baba ńlá rẹ̀, wọ́n sì sin ín pẹ̀lú àwọn baba ńlá rẹ̀ sí Ìlú Dáfídì.+ Ahasáyà+ ọmọ rẹ̀ sì jọba ní ipò rẹ̀.
25 Ní ọdún kejìlá Jèhórámù ọmọ Áhábù ọba Ísírẹ́lì, Ahasáyà ọmọ Jèhórámù ọba Júdà di ọba.+ 26 Ẹni ọdún méjìlélógún (22) ni Ahasáyà nígbà tó jọba, ọdún kan ló sì fi ṣàkóso ní Jerúsálẹ́mù. Orúkọ ìyá rẹ̀ ni Ataláyà+ ọmọ ọmọ* Ómírì+ ọba Ísírẹ́lì. 27 Ó ń ṣe ohun tí àwọn ará ilé Áhábù+ ṣe, ó sì ń ṣe ohun tó burú ní ojú Jèhófà bí ilé Áhábù ti ṣe, nítorí ó fẹ́ ìyàwó ní ilé Áhábù.+ 28 Torí náà, ó bá Jèhórámù ọmọ Áhábù lọ láti gbéjà ko Hásáẹ́lì ọba Síríà ní Ramoti-gílíádì,+ ṣùgbọ́n àwọn ará Síríà ṣe Jèhórámù léṣe.+ 29 Nítorí náà, Ọba Jèhórámù pa dà sí Jésírẹ́lì+ kó lè tọ́jú ọgbẹ́ tí àwọn ará Síríà dá sí i lára ní Rámà nígbà tó ń bá Hásáẹ́lì ọba Síríà jà.+ Ahasáyà ọmọ Jèhórámù ọba Júdà lọ wo Jèhórámù ọmọ Áhábù ní Jésírẹ́lì, torí wọ́n ti ṣe é léṣe.*
9 Lẹ́yìn náà, wòlíì Èlíṣà pe ọ̀kan lára àwọn ọmọ wòlíì, ó sì sọ fún un pé: “Ká aṣọ rẹ mọ́ra, kí o sì yára mú ṣágo* òróró yìí lọ sí Ramoti-gílíádì.+ 2 Tí o bá ti dé ibẹ̀, kí o wá Jéhù+ ọmọ Jèhóṣáfátì ọmọ Nímúṣì; wọlé lọ bá a, kí o ní kó dìde kúrò láàárín àwọn arákùnrin rẹ̀, kí o sì mú un lọ sínú yàrá inú lọ́hùn-ún. 3 Kí o mú ṣágo òróró náà, kí o sì dà á sí i lórí, kí o wá sọ pé, ‘Ohun tí Jèhófà sọ nìyí: “Mo fòróró yàn ọ́ ṣe ọba lórí Ísírẹ́lì.”’+ Lẹ́yìn náà, ṣí ilẹ̀kùn, kí o sì tètè sá lọ.”
4 Torí náà, ìránṣẹ́ wòlíì náà bọ́ sọ́nà, ó sì forí lé Ramoti-gílíádì. 5 Nígbà tó dé ibẹ̀, àwọn olórí ọmọ ogun wà ní ìjókòó. Ló bá sọ pé: “Iṣẹ́ kan wà tí wọ́n ní kí n jẹ́ fún ọ, balógun.” Jéhù béèrè pé: “Èwo nínú wa?” Ó dáhùn pé: “Balógun, ìwọ ni.” 6 Nítorí náà, Jéhù dìde, ó wọnú ilé; ìránṣẹ́ náà da òróró sí i lórí, ó sì sọ fún un pé,“Ohun tí Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì sọ nìyí: ‘Mo fòróró yàn ọ́ ṣe ọba lórí àwọn èèyàn Jèhófà, lórí Ísírẹ́lì.+ 7 Kí o pa àwọn ará ilé Áhábù olúwa rẹ, màá sì gbẹ̀san ẹ̀jẹ̀ àwọn ìránṣẹ́ mi wòlíì àti ti gbogbo ìránṣẹ́ Jèhófà tí Jésíbẹ́lì pa.+ 8 Gbogbo ilé Áhábù ló máa ṣègbé; màá sì pa gbogbo ọkùnrin* ilé Áhábù run, títí kan àwọn aláìní àti àwọn aláìníláárí ní Ísírẹ́lì.+ 9 Màá ṣe ilé Áhábù bí ilé Jèróbóámù+ ọmọ Nébátì àti bí ilé Bááṣà+ ọmọ Áhíjà. 10 Ní ti Jésíbẹ́lì, àwọn ajá ló máa jẹ ẹ́ ní ilẹ̀ tó wà ní Jésírẹ́lì,+ ẹnì kankan ò ní sin ín.’” Ló bá ṣí ilẹ̀kùn, ó sì sá lọ.+
11 Nígbà tí Jéhù pa dà sọ́dọ̀ àwọn ìránṣẹ́ olúwa rẹ̀, wọ́n béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé: “Ṣé kò sí o? Kí nìdí tí ayírí yìí fi wá bá ọ?” Ó dá wọn lóhùn pé: “Ẹ̀yin náà mọ irú èèyàn tí ọkùnrin náà jẹ́, ẹ sì mọ ohun tí irú wọn máa ń sọ.” 12 Ṣùgbọ́n wọ́n sọ pé: “Irọ́ ni! Jọ̀ọ́, sòótọ́ fún wa.” Nígbà náà, ó sọ pé: “Báyìí-báyìí ló sọ fún mi, ó sì fi kún un pé, ‘Ohun tí Jèhófà sọ nìyí: “Mo fòróró yàn ọ́ ṣe ọba lórí Ísírẹ́lì.”’”+ 13 Ní kíá, kálukú mú aṣọ rẹ̀, wọ́n sì tẹ́ ẹ sórí àtẹ̀gùn kó lè gun orí rẹ̀,+ wọ́n fun ìwo, wọ́n sì sọ pé: “Jéhù ti di ọba!”+ 14 Lẹ́yìn náà, Jéhù+ ọmọ Jèhóṣáfátì ọmọ Nímúṣì dìtẹ̀ sí Jèhórámù.
Ní àkókò yẹn, Jèhórámù àti gbogbo Ísírẹ́lì wà ní Ramoti-gílíádì,+ wọn ò sì dẹra nù nítorí Hásáẹ́lì+ ọba Síríà. 15 Nígbà tó yá, ọba Jèhórámù pa dà sí Jésírẹ́lì+ kó lè tọ́jú ọgbẹ́ tí àwọn ará Síríà dá sí i lára nígbà tó bá Hásáẹ́lì ọba Síríà+ jà.
Ni Jéhù bá sọ pé: “Bí ẹ* bá gbà pẹ̀lú mi, ẹ má ṣe jẹ́ kí ẹnikẹ́ni sá kúrò ní ìlú láti lọ ròyìn ní Jésírẹ́lì.” 16 Lẹ́yìn náà, Jéhù gun kẹ̀kẹ́ ẹṣin rẹ̀, ó sì lọ sí Jésírẹ́lì, torí ibẹ̀ ni Jèhórámù dùbúlẹ̀ sí pẹ̀lú ọgbẹ́ lára, Ahasáyà ọba Júdà sì wá wo Jèhórámù níbẹ̀. 17 Bí olùṣọ́ ṣe dúró sórí ilé gogoro tó wà ní Jésírẹ́lì, ó rí ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ àwọn ọkùnrin Jéhù tí wọ́n ń bọ̀. Ní kíá, ó sọ pé: “Mo rí ọ̀pọ̀ èèyàn tó ń bọ̀.” Jèhórámù bá sọ pé: “Mú agẹṣinjagun kan, kí o rán an lọ pàdé wọn, kó sì béèrè pé, ‘Ṣé àlàáfíà lẹ bá wá?’” 18 Torí náà, agẹṣin kan lọ pàdé rẹ̀, ó sì sọ pé: “Ọba ní kí n bi yín pé, ‘Ṣé àlàáfíà lẹ bá wá?’” Ṣùgbọ́n Jéhù sọ pé: “Ọ̀rọ̀ ‘àlàáfíà’ wo lò ń sọ? Bọ́ sẹ́yìn mi!”
Olùṣọ́ wá ròyìn pé: “Òjíṣẹ́ náà dé ọ̀dọ̀ wọn, ṣùgbọ́n kò tíì pa dà.” 19 Nítorí náà, ó rán agẹṣin kejì jáde, nígbà tó dé ọ̀dọ̀ wọn, ó sọ pé: “Ọba ní kí n bi yín pé, ‘Ṣé àlàáfíà lẹ bá wá?’” Àmọ́ Jéhù sọ pé: “Ọ̀rọ̀ ‘àlàáfíà’ wo lò ń sọ? Bọ́ sẹ́yìn mi!”
20 Lẹ́yìn náà, olùṣọ́ ròyìn pé: “Ó dé ọ̀dọ̀ wọn, ṣùgbọ́n kò tíì pa dà, bó ṣe ń gun kẹ̀kẹ́ ẹṣin rẹ̀ sì dà bíi ti Jéhù ọmọ ọmọ* Nímúṣì, nítorí eré àsápajúdé ló máa ń sá.” 21 Jèhórámù sọ pé: “Di kẹ̀kẹ́ ẹṣin!” Nítorí náà, wọ́n di kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀, Jèhórámù ọba Ísírẹ́lì àti Ahasáyà+ ọba Júdà sì jáde lọ, kálukú nínú kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀ láti pàdé Jéhù. Wọ́n bá a pàdé ní ilẹ̀ Nábótì+ ará Jésírẹ́lì.
22 Bí Jèhórámù ṣe rí Jéhù, ó sọ pé: “Ṣé àlàáfíà lo bá wá, Jéhù?” Àmọ́, ó sọ pé: “Àlàáfíà báwo, nígbà tó jẹ́ pé Jésíbẹ́lì+ ìyá rẹ kò jáwọ́ nínú ìṣekúṣe àti ọ̀pọ̀ iṣẹ́ àjẹ́ rẹ̀?”+ 23 Lójú ẹsẹ̀, Jèhórámù yíjú kẹ̀kẹ́ ẹṣin rẹ̀ pa dà kó lè sá lọ, ó sì sọ fún Ahasáyà pé: “Wọ́n ti tàn wá, Ahasáyà!” 24 Jéhù mú ọfà,* ó sì ta á lu Jèhórámù ní àárín méjì ẹ̀yìn rẹ̀, ọfà náà jáde ní ọkàn rẹ̀, ó sì ṣubú sínú kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀. 25 Jéhù wá sọ fún Bídíkárì tó jẹ́ olùrànlọ́wọ́ rẹ̀ lójú ogun pé: “Gbé e, kí o sì jù ú sínú ilẹ̀ Nábótì ará Jésírẹ́lì.+ Rántí pé èmi pẹ̀lú rẹ jọ ń gun ẹṣin* tẹ̀ lé Áhábù bàbá rẹ̀ nígbà tí Jèhófà fúnra rẹ̀ kéde ìdájọ́ lé e lórí pé:+ 26 ‘“Bí mo ṣe rí ẹ̀jẹ̀ Nábótì+ àti ẹ̀jẹ̀ àwọn ọmọ rẹ̀ lánàá,” ni Jèhófà wí, “màá san án pa dà+ fún ọ ní ilẹ̀ yìí kan náà,” ni Jèhófà wí.’ Torí náà, gbé e, kí o sì jù ú sórí ilẹ̀ náà gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ tí Jèhófà sọ.”+
27 Nígbà tí Ahasáyà+ ọba Júdà rí ohun tó ń ṣẹlẹ̀, ó sá gba ọ̀nà ilé ọgbà. (Lẹ́yìn náà, Jéhù lépa rẹ̀, ó sì sọ pé: “Ẹ pa òun náà!” Torí náà, wọ́n ṣe é léṣe nínú kẹ̀kẹ́ ẹṣin rẹ̀ bó ṣe ń lọ sí Gúrì tó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ Íbíléámù.+ Àmọ́ kò dúró títí ó fi sá dé Mẹ́gídò, ó sì kú síbẹ̀. 28 Lẹ́yìn ìyẹn, àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ fi kẹ̀kẹ́ ẹṣin gbé e lọ sí Jerúsálẹ́mù, wọ́n sì sin ín sí sàréè rẹ̀ pẹ̀lú àwọn baba ńlá rẹ̀ ní Ìlú Dáfídì.+ 29 Ọdún kọkànlá Jèhórámù ọmọ Áhábù ni Ahasáyà + di ọba lórí Júdà.)
30 Nígbà tí Jéhù dé Jésírẹ́lì,+ Jésíbẹ́lì+ gbọ́ pé ó ti dé. Torí náà, ó lé tìróò* sójú, ó ṣe irun rẹ̀ lóge, ó sì bojú wolẹ̀ látojú fèrèsé.* 31 Bí Jéhù ṣe ń gba ẹnubodè wọlé, Jésíbẹ́lì sọ pé: “Ǹjẹ́ ó dáa fún Símírì, ẹni tó pa olúwa rẹ̀?”+ 32 Bí Jéhù ṣe gbójú sókè wo fèrèsé náà, ó sọ pé: “Ta ló wà lẹ́yìn mi nínú yín? Ta ni?”+ Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, àwọn méjì sí mẹ́ta tó jẹ́ òṣìṣẹ́ ààfin yọjú wò ó látòkè. 33 Ó sọ pé: “Ẹ jù ú sísàlẹ̀!” Torí náà, wọ́n jù ú sísàlẹ̀, lára ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ sì ta sára ògiri àti sára àwọn ẹṣin, àwọn ẹṣin Jéhù sì tẹ̀ ẹ́ mọ́lẹ̀. 34 Lẹ́yìn náà, ó wọlé, ó jẹ, ó sì mu. Ó wá sọ pé: “Ẹ jọ̀ọ́, ẹ palẹ̀ obìnrin ẹni ègún yìí mọ́, kí ẹ sì sin ín. Ó ṣe tán, ọmọ ọba ni.”+ 35 Àmọ́ nígbà tí wọ́n fẹ́ lọ sin ín, agbárí rẹ̀ àti ẹsẹ̀ rẹ̀ pẹ̀lú àwọn àtẹ́lẹwọ́ rẹ̀ nìkan ló ṣẹ́ kù tí wọ́n rí.+ 36 Nígbà tí wọ́n pa dà tí wọ́n sì sọ fún un, ó sọ pé: “Ọ̀rọ̀ Jèhófà ló ṣẹ,+ èyí tó gbẹnu Èlíjà ará Tíṣíbè ìránṣẹ́ rẹ̀ sọ pé, ‘Orí ilẹ̀ tó wà ní Jésírẹ́lì ni àwọn ajá ti máa jẹ ẹran ara Jésíbẹ́lì.+ 37 Òkú Jésíbẹ́lì yóò sì di ajílẹ̀ lórí ilẹ̀ tó wà ní Jésírẹ́lì, tí ẹnikẹ́ni ò fi ní lè sọ pé: “Jésíbẹ́lì nìyí.”’”
10 Áhábù+ ní àádọ́rin (70) ọmọkùnrin ní Samáríà. Nítorí náà, Jéhù kọ àwọn lẹ́tà, ó sì fi wọ́n ránṣẹ́ sí Samáríà, sí àwọn ìjòyè Jésírẹ́lì, àwọn àgbààgbà+ àti àwọn tó ń tọ́jú àwọn ọmọ Áhábù,* ó sọ pé: 2 “Bí lẹ́tà yìí bá ṣe ń tẹ̀ yín lọ́wọ́, àwọn ọmọkùnrin olúwa yín máa wà lọ́dọ̀ yín àti àwọn kẹ̀kẹ́ ogun, àwọn ẹṣin pẹ̀lú àwọn ohun ìjà, ẹ sì wà nínú ìlú olódi. 3 Kí ẹ yan èyí tó bá dára jù, tó sì yẹ* lára àwọn ọmọkùnrin olúwa yín, kí ẹ sì gbé e gorí ìtẹ́ bàbá rẹ̀. Lẹ́yìn náà, kí ẹ jà fún ilé olúwa yín.”
4 Àmọ́ ẹ̀rù bà wọ́n gidigidi, wọ́n sì sọ pé: “Ẹ wò ó! Tí ọba méjì kò bá lè dúró níwájú rẹ̀,+ báwo ni àwa ṣe lè dúró?” 5 Torí náà, alábòójútó ààfin,* gómìnà ìlú, àwọn àgbààgbà àti àwọn olùtọ́jú ránṣẹ́ sí Jéhù pé: “Ìránṣẹ́ rẹ ni wá, a ó sì ṣe gbogbo ohun tí o bá sọ fún wa. A ò ní fi ẹnì kankan jẹ ọba. Ohun tó bá dára ní ojú rẹ ni kí o ṣe.”
6 Ló bá kọ lẹ́tà kejì sí wọn, ó ní: “Tó bá jẹ́ pé tèmi lẹ̀ ń ṣe, tó sì wù yín láti ṣègbọràn sí mi, ẹ kó orí àwọn ọmọkùnrin olúwa yín, kí ẹ sì wá bá mi ní Jésírẹ́lì ní ìwòyí ọ̀la.”
Lákòókò yìí, àádọ́rin (70) àwọn ọmọkùnrin ọba wà lọ́dọ̀ àwọn sàràkí ọkùnrin ìlú, ìyẹn àwọn tó ń tọ́ wọn. 7 Gbàrà tí lẹ́tà náà tẹ̀ wọ́n lọ́wọ́, wọ́n kó àwọn ọmọkùnrin ọba, wọ́n sì pa wọ́n, àwọn àádọ́rin (70) ọkùnrin,+ wọ́n kó orí wọn sínú apẹ̀rẹ̀, wọ́n sì kó wọn ránṣẹ́ sí i ní Jésírẹ́lì. 8 Òjíṣẹ́ náà wọlé, ó sì sọ fún un pé: “Wọ́n ti kó orí àwọn ọmọkùnrin ọba dé.” Torí náà, ó sọ pé: “Ẹ kó wọn jọ ní òkìtì méjì sí ibi àtiwọ ẹnubodè ìlú títí di àárọ̀.” 9 Nígbà tó jáde ní àárọ̀, ó dúró níwájú gbogbo àwọn èèyàn náà, ó sì sọ pé: “Ẹ ò ní ẹ̀bi kankan.* Òótọ́ ni pé mo ṣọ̀tẹ̀ sí olúwa mi, mo sì pa á,+ àmọ́ ta ló pa gbogbo àwọn yìí? 10 Torí náà, ẹ mọ̀ dájú pé kò sí ìkankan nínú ọ̀rọ̀ Jèhófà tí Jèhófà kéde sórí ilé Áhábù tí kò ní ṣẹ,*+ Jèhófà sì ti ṣe ohun tó gbẹnu ìránṣẹ́ rẹ̀ Èlíjà sọ.”+ 11 Yàtọ̀ síyẹn, Jéhù pa gbogbo àwọn tó ṣẹ́ kù ní ilé Áhábù ní Jésírẹ́lì, títí kan gbogbo sàràkí ọkùnrin rẹ̀, àwọn ojúlùmọ̀ rẹ̀ àti àwọn àlùfáà rẹ̀,+ kò jẹ́ kí èèyàn rẹ̀ kankan ṣẹ́ kù.+
12 Lẹ́yìn náà, ó dìde, ó sì forí lé Samáríà. Ilé tí àwọn olùṣọ́ àgùntàn ti ń so àgùntàn mọ́lẹ̀* wà lójú ọ̀nà. 13 Ibẹ̀ ni Jéhù ti bá àwọn arákùnrin Ahasáyà+ ọba Júdà pàdé, ó béèrè lọ́wọ́ wọn pé, “Ta ni yín?” Wọ́n sọ pé: “Arákùnrin Ahasáyà ni wá, a fẹ́ lọ béèrè àlàáfíà àwọn ọmọ ọba àti àwọn ọmọ ìyá ọba.”* 14 Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, ó sọ pé: “Ẹ mú wọn láàyè!” Torí náà, wọ́n mú wọn láàyè, wọ́n sì pa wọ́n níbi kòtò omi tó wà ní ilé tí wọ́n ti ń so àgùntàn mọ́lẹ̀, gbogbo àwọn ọkùnrin náà jẹ́ méjìlélógójì (42). Kò sì jẹ́ kí ìkankan lára wọn ṣẹ́ kù.+
15 Bó ṣe kúrò níbẹ̀, ó bá Jèhónádábù+ ọmọ Rékábù+ pàdé tó ń bọ̀ wá bá a. Nígbà tó kí i,* ó sọ fún un pé: “Ṣé gbogbo ọkàn rẹ wà* pẹ̀lú mi bí ọkàn mi ṣe wà pẹ̀lú ọkàn rẹ?”
Jèhónádábù fèsì pé: “Bẹ́ẹ̀ ni.”
Jéhù wá sọ pé: “Tó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, fún mi ní ọwọ́ rẹ.”
Torí náà, ó na ọwọ́ sí i, Jéhù sì fà á gòkè sínú kẹ̀kẹ́ ẹṣin rẹ̀. 16 Ló bá sọ pé: “Bá mi ká lọ, kí o sì rí bí mi ò ṣe fàyè gba bíbá Jèhófà díje.”*+ Torí náà, wọ́n mú un wọnú kẹ́kẹ́ ogun rẹ̀, wọ́n sì jọ ń lọ. 17 Nígbà tí wọ́n dé Samáríà, ó pa gbogbo àwọn tó ṣẹ́ kù ní ilé Áhábù ní Samáríà, títí ó fi pa gbogbo wọn run,+ gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ tí Jèhófà sọ fún Èlíjà.+
18 Bákan náà, Jéhù kó gbogbo àwọn èèyàn náà jọ, ó sì sọ fún wọn pé: “Áhábù jọ́sìn Báálì díẹ̀,+ àmọ́ Jéhù yóò jọ́sìn rẹ̀ lọ́pọ̀lọpọ̀. 19 Torí náà, ẹ pe gbogbo àwọn wòlíì Báálì,+ gbogbo àwọn tó ń jọ́sìn rẹ̀ àti gbogbo àwọn àlùfáà rẹ̀+ wá sọ́dọ̀ mi. Ẹ rí i dájú pé gbogbo wọn ló wá, nítorí mo fẹ́ rú ẹbọ ńlá sí Báálì. Ẹnikẹ́ni tí kò bá wá máa kú.” Àmọ́, ńṣe ni Jéhù ń lo ọgbọ́n ẹ̀wẹ́ láti pa àwọn tó ń jọ́sìn Báálì run.
20 Jéhù ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ pé: “Ẹ kéde àpéjọ ọlọ́wọ̀ kan* fún Báálì.” Torí náà, wọ́n kéde rẹ̀. 21 Lẹ́yìn ìyẹn, Jéhù ránṣẹ́ káàkiri gbogbo Ísírẹ́lì, gbogbo àwọn tó ń jọ́sìn Báálì sì wá. Kò sí ìkankan lára wọn tó ṣẹ́ kù tí kò wá. Wọ́n wọ ilé* Báálì,+ ilé Báálì sì kún láti ìpẹ̀kun kan dé ìpẹ̀kun kejì. 22 Ó sọ fún ẹni tó wà nídìí ibi tí wọ́n ń kó aṣọ sí pé: “Kó aṣọ jáde fún gbogbo àwọn tó ń jọ́sìn Báálì.” Torí náà, ó kó aṣọ jáde fún wọn. 23 Lẹ́yìn náà, Jéhù àti Jèhónádábù+ ọmọ Rékábù wọ inú ilé Báálì. Ó wá sọ fún àwọn tó ń jọ́sìn Báálì pé: “Ẹ fara balẹ̀ wá ibí yìí dáadáa pé kò sí olùjọsìn Jèhófà kankan níbí, àfi àwọn olùjọsìn Báálì nìkan.” 24 Níkẹyìn, wọ́n wọlé láti rú àwọn ẹbọ àti ẹbọ sísun. Àmọ́ Jéhù ti yan ọgọ́rin (80) lára àwọn ọkùnrin rẹ̀ síta, ó ní: “Tí ìkankan lára àwọn ọkùnrin tí mo fi sí ìkáwọ́ yín bá lọ pẹ́nrẹ́n, ẹ̀mí* yín lẹ máa fi dí i.”
25 Gbàrà tí Jéhù rú ẹbọ sísun náà tán, ó sọ fún àwọn ẹ̀ṣọ́* àti àwọn olùrànlọ́wọ́ ọ̀gágun pé: “Ẹ wọlé, kí ẹ sì ṣá wọn balẹ̀! Ẹ má ṣe jẹ́ kí ìkankan lára wọn lọ!”+ Torí náà, àwọn ẹ̀ṣọ́ àti àwọn olùrànlọ́wọ́ ọ̀gágun fi idà ṣá wọn balẹ̀, wọ́n gbé òkú wọn jù síta, wọ́n sì ń lọ títí dé ibi mímọ́* ilé Báálì. 26 Nígbà náà, wọ́n kó àwọn ọwọ̀n òrìṣà+ tó wà ní ilé Báálì jáde, wọ́n sì dáná sun wọ́n lọ́kọ̀ọ̀kan.+ 27 Wọ́n ti ọwọ̀n òrìṣà Báálì ṣubú,+ wọ́n wó ilé Báálì+ lulẹ̀, wọ́n sì sọ ọ́ di ilé ìyàgbẹ́, bó ṣe wà títí di òní yìí.
28 Bí Jéhù ṣe pa Báálì rẹ́ ní Ísírẹ́lì nìyẹn. 29 Àmọ́, Jéhù ò kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ tí Jèróbóámù ọmọ Nébátì mú kí Ísírẹ́lì dá, ìyẹn jíjọ́sìn àwọn ọmọ màlúù wúrà tó wà ní Bẹ́tẹ́lì àti Dánì.+ 30 Torí náà, Jèhófà sọ fún Jéhù pé: “Nítorí pé o ṣe dáadáa, tí o sì ṣe ohun tí ó tọ́ lójú mi, bí o ṣe ṣe gbogbo ohun tó wà lọ́kàn mi sí ilé Áhábù,+ àwọn ọmọ rẹ títí dé ìran kẹrin yóò máa jókòó lórí ìtẹ́ Ísírẹ́lì.”+ 31 Àmọ́ Jéhù ò kíyè sára láti fi gbogbo ọkàn rẹ̀ pa Òfin Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì mọ́.+ Kò kúrò nínú àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tí Jèróbóámù mú kí Ísírẹ́lì dá.+
32 Lákòókò yẹn, Jèhófà bẹ̀rẹ̀ sí í gé* ìpínlẹ̀ Ísírẹ́lì kù. Hásáẹ́lì ń kọ lù wọ́n léraléra káàkiri ìpínlẹ̀ Ísírẹ́lì,+ 33 láti Jọ́dánì sápá ìlà oòrùn, gbogbo ilẹ̀ Gílíádì, níbi tí ẹ̀yà Gádì, ẹ̀yà Rúbẹ́nì àti ẹ̀yà Mánásè+ ń gbé. Ìpínlẹ̀ Áróérì tó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ Àfonífojì Áánónì títí dé Gílíádì àti Báṣánì wà lára wọn.+
34 Ní ti ìyókù ìtàn Jéhù àti gbogbo ohun tí ó ṣe àti gbogbo agbára rẹ̀, ǹjẹ́ kò wà lákọsílẹ̀ nínú ìwé ìtàn ìgbà àwọn ọba Ísírẹ́lì? 35 Níkẹyìn, Jéhù sinmi pẹ̀lú àwọn baba ńlá rẹ̀, wọ́n sì sin ín sí Samáríà; Jèhóáhásì+ ọmọ rẹ̀ sì jọba ní ipò rẹ̀. 36 Àkókò* tí Jéhù fi jọba lórí Ísírẹ́lì jẹ́ ọdún méjìdínlọ́gbọ̀n (28) ní Samáríà.
11 Nígbà tí Ataláyà,+ ìyá Ahasáyà rí i pé ọmọ òun ti kú,+ ó dìde, ó sì pa gbogbo ìdílé ọba* run.+ 2 Àmọ́, Jèhóṣébà ọmọbìnrin Ọba Jèhórámù, arábìnrin Ahasáyà, gbé Jèhóáṣì+ ọmọ Ahasáyà, ó jí i gbé láàárín àwọn ọmọ ọba tí wọ́n fẹ́ pa, ó fi òun àti obìnrin tó ń tọ́jú rẹ̀ pa mọ́ sínú yàrá inú lọ́hùn-ún. Wọ́n sì rọ́nà fi í pa mọ́ kí Ataláyà má bàa rí i, torí náà kò rí i pa. 3 Ọdún mẹ́fà ló fi wà lọ́dọ̀ rẹ̀, ó tọ́jú rẹ̀ pa mọ́ sí ilé Jèhófà nígbà tí Ataláyà ń ṣàkóso ilẹ̀ náà.
4 Ní ọdún keje, Jèhóádà ránṣẹ́ sí àwọn olórí ọgọ́rọ̀ọ̀rún ẹ̀ṣọ́ Káríà àti àwọn ẹ̀ṣọ́ ààfin,*+ ó ní kí wọ́n wá bá òun ní ilé Jèhófà. Ó bá wọn ṣe àdéhùn,* ó sì ní kí wọ́n búra sí i ní ilé Jèhófà, lẹ́yìn náà ó fi ọmọ ọba hàn wọ́n.+ 5 Ó pàṣẹ fún wọn pé: “Ohun tí ẹ máa ṣe nìyí: Ìdá mẹ́ta yín á wà lẹ́nu iṣẹ́ ní Sábáàtì, ẹ ó sì máa ṣọ́ ilé* ọba+ lójú méjèèjì, 6 ìdá mẹ́ta míì á wà ní Ẹnubodè Ìpìlẹ̀, ìdá mẹ́ta míì á sì wà ní ẹnubodè tó wà lẹ́yìn àwọn ẹ̀ṣọ́ ààfin. Kí ẹ máa ṣe iṣẹ́ ṣíṣọ́ ilé náà ní àṣegbà. 7 Ìdá méjì tí kò ní sí lẹ́nu iṣẹ́ ní ọjọ́ Sábáàtì ní láti máa ṣọ́ ilé Jèhófà lójú méjèèjì láti dáàbò bo ọba. 8 Kí ẹ yí ọba ká, kálukú pẹ̀lú àwọn ohun ìjà rẹ̀ lọ́wọ́. Ẹni tó bá wọlé wá sáàárín àwọn ọmọ ogun ni a ó pa. Ẹ dúró ti ọba níbikíbi tó bá lọ.”*
9 Àwọn olórí ọgọ́rọ̀ọ̀rún+ ṣe ohun tí àlùfáà Jèhóádà pa láṣẹ fún wọn gẹ́lẹ́. Torí náà, kálukú mú àwọn ọkùnrin rẹ̀ tó wà lẹ́nu iṣẹ́ ní Sábáàtì pẹ̀lú àwọn tí kò sí lẹ́nu iṣẹ́ ní Sábáàtì, wọ́n sì wá sọ́dọ̀ àlùfáà Jèhóádà.+ 10 Àlùfáà wá fún àwọn olórí ọgọ́rọ̀ọ̀rún ní àwọn ọ̀kọ̀ àti apata* tó jẹ́ ti Ọba Dáfídì, tó wà ní ilé Jèhófà. 11 Àwọn ẹ̀ṣọ́ ààfin+ wà ní ìdúró, kálukú pẹ̀lú ohun ìjà rẹ̀ lọ́wọ́, láti apá ọ̀tún ilé náà títí dé apá òsì ilé náà, lẹ́gbẹ̀ẹ́ pẹpẹ+ àti lẹ́gbẹ̀ẹ́ ilé náà, gbogbo wọn yí ọba ká. 12 Lẹ́yìn náà Jèhóádà mú ọmọ ọba+ jáde, ó fi adé* dé e, ó si fi Ẹ̀rí*+ sí i lórí, wọ́n fi jọba, wọ́n sì fòróró yàn án. Wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í pàtẹ́wọ́, wọ́n sì ń sọ pé: “Kí ẹ̀mí ọba ó gùn o!”+
13 Nígbà tí Ataláyà gbọ́ ìró àwọn èèyàn tó ń sáré, ní kíá, ó lọ bá àwọn èèyàn tó wà ní ilé Jèhófà.+ 14 Ó wá rí ọba níbẹ̀ tó dúró sẹ́gbẹ̀ẹ́ òpó gẹ́gẹ́ bí ìṣe àwọn ọba.+ Àwọn olórí àti àwọn tó ń fun kàkàkí+ wà lọ́dọ̀ ọba, gbogbo àwọn èèyàn ilẹ̀ náà ń yọ̀, wọ́n sì ń fun kàkàkí. Ni Ataláyà bá fa aṣọ ara rẹ̀ ya, ó sì kígbe pé: “Ọ̀tẹ̀ rèé o! Ọ̀tẹ̀ rèé o!” 15 Àmọ́ àlùfáà Jèhóádà pàṣẹ fún àwọn olórí ọgọ́rọ̀ọ̀rún,+ àwọn tí a yàn ṣe olórí ọmọ ogun, ó sì sọ fún wọn pé: “Ẹ mú un kúrò láàárín àwọn ọmọ ogun, tí ẹnikẹ́ni bá sì tẹ̀ lé e, kí ẹ fi idà pa á!” Nítorí àlùfáà ti sọ pé: “Ẹ má ṣe pa á ní ilé Jèhófà.” 16 Torí náà, wọ́n mú un, nígbà tó sì dé ibi tí ẹṣin ti máa ń wọ ilé* ọba,+ wọ́n pa á níbẹ̀.
17 Lẹ́yìn náà, Jèhóádà dá májẹ̀mú láàárín Jèhófà àti ọba àti àwọn èèyàn náà,+ pé àwọn á máa jẹ́ èèyàn Jèhófà nìṣó, ó sì tún dá májẹ̀mú láàárín ọba àti àwọn èèyàn náà.+ 18 Lẹ́yìn ìyẹn, gbogbo àwọn èèyàn ilẹ̀ náà wá sí ilé* Báálì, wọ́n wó àwọn pẹpẹ rẹ̀ lulẹ̀,+ wọ́n fọ́ àwọn ère rẹ̀ túútúú,+ wọ́n sì pa Mátánì àlùfáà Báálì+ níwájú àwọn pẹpẹ náà.
Àlùfáà wá yan àwọn alábòójútó lórí ilé Jèhófà.+ 19 Yàtọ̀ síyẹn, ó kó àwọn olórí ọgọ́rọ̀ọ̀rún,+ àwọn ẹ̀ṣọ́ Káríà àti àwọn ẹ̀ṣọ́ ààfin+ pẹ̀lú gbogbo àwọn èèyàn ilẹ̀ náà kí wọ́n lè tẹ̀ lé ọba láti ilé Jèhófà, wọ́n sì gba ọ̀nà ẹnubodè ẹ̀ṣọ́ ààfin wá sí ilé* ọba. Ó wá jókòó sórí ìtẹ́ ọba.+ 20 Torí náà, gbogbo àwọn èèyàn ilẹ̀ náà ń yọ̀, ìlú náà sì tòrò, nítorí pé wọ́n ti pa* Ataláyà ní ilé ọba.
21 Ọmọ ọdún méje ni Jèhóáṣì+ nígbà tó jọba.+
12 Ní ọdún keje Jéhù,+ Jèhóáṣì+ di ọba, ó sì fi ogójì (40) ọdún ṣàkóso ní Jerúsálẹ́mù. Orúkọ ìyá rẹ̀ ni Sibáyà láti Bíá-ṣébà.+ 2 Jèhóáṣì ń ṣe ohun tí ó tọ́ lójú Jèhófà ní gbogbo ìgbà tí àlùfáà Jèhóádà fi ń tọ́ ọ sọ́nà. 3 Àmọ́ kò mú àwọn ibi gíga+ kúrò, àwọn èèyàn náà ṣì ń rúbọ, wọ́n sì ń mú ẹbọ rú èéfín ní àwọn ibi gíga.
4 Jèhóáṣì sọ fún àwọn àlùfáà pé: “Ẹ gba gbogbo owó tó jẹ́ ọrẹ mímọ́+ tí wọ́n bá mú wá sí ilé Jèhófà, ìyẹn owó tí wọ́n ní kí ẹnì kọ̀ọ̀kan mú wá,+ owó tí àwọn àlùfáà gbà lọ́wọ́ àwọn* tó jẹ́ ẹ̀jẹ́ àti gbogbo owó tó bá wá látọkàn kálukú láti mú wá sí ilé Jèhófà.+ 5 Àwọn àlùfáà yóò fúnra wọn gbà á lọ́wọ́ àwọn tó ń dáwó fún wọn,* wọ́n á sì lò ó láti fi ṣàtúnṣe ibikíbi tí wọ́n bá rí pé ó bà jẹ́* lára ilé náà.”+
6 Títí di ọdún kẹtàlélógún Ọba Jèhóáṣì, àwọn àlùfáà kò tíì ṣàtúnṣe àwọn ibi tó bà jẹ́ lára ilé náà.+ 7 Torí náà, Ọba Jèhóáṣì pe àlùfáà Jèhóádà+ àti àwọn àlùfáà yòókù, ó sì sọ fún wọn pé: “Kí ló dé tí ẹ kò fi ṣàtúnṣe àwọn ibi tó bà jẹ́ lára ilé náà? Ní báyìí, ẹ má gba owó kankan mọ́ lọ́wọ́ àwọn tó ń dáwó fún yín àfi tí ẹ bá máa lò ó láti ṣàtúnṣe ilé náà.”+ 8 Torí náà, àwọn àlùfáà gbà pé àwọn ò ní gba owó lọ́wọ́ àwọn èèyàn náà mọ́ àti pé àwọn ò ní tún ilé náà ṣe.
9 Ni àlùfáà Jèhóádà bá gbé àpótí kan,+ ó lu ihò sí ọmọrí rẹ̀, ó sì gbé e sí ẹ̀gbẹ́ pẹpẹ lápá ọ̀tún téèyàn bá wọ inú ilé Jèhófà. Ibẹ̀ ni àwọn àlùfáà tó ń ṣọ́ ẹnu ọ̀nà máa ń kó gbogbo owó tí àwọn èèyàn bá mú wá sí ilé Jèhófà sí.+ 10 Nígbàkigbà tí wọ́n bá rí i pé owó ti pọ̀ nínú àpótí náà, akọ̀wé ọba àti àlùfáà àgbà á wá, wọ́n á kó owó náà,* wọ́n á sì ka owó tí àwọn èèyàn mú wá sí ilé Jèhófà.+ 11 Wọ́n á kó owó tí wọ́n kà náà fún àwọn tí wọ́n yàn láti máa bójú tó iṣẹ́ ilé Jèhófà. Àwọn, ní tiwọn á wá san án fún àwọn oníṣẹ́ igi àti àwọn kọ́lékọ́lé tó ń ṣiṣẹ́ ní ilé Jèhófà,+ 12 títí kan àwọn mọlémọlé àti àwọn agbẹ́kùúta. Wọ́n tún ra ẹ̀là gẹdú àti òkúta gbígbẹ́ láti fi ṣàtúnṣe àwọn ibi tó bà jẹ́ lára ilé Jèhófà, wọ́n sì ná owó náà sórí àwọn àtúnṣe míì tó jẹ mọ́ ilé náà.
13 Àmọ́, wọn kò fi ìkankan lára owó tí àwọn èèyàn mú wá sí ilé Jèhófà ṣe àwọn bàsíà fàdákà, àwọn ohun tí wọ́n fi ń pa fìtílà, àwọn abọ́, àwọn kàkàkí+ tàbí ohun èlò èyíkéyìí tó jẹ́ wúrà tàbí fàdákà láti lò wọ́n ní ilé Jèhófà.+ 14 Àwọn tó ń ṣe iṣẹ́ náà nìkan ni wọ́n ń fún ní owó náà, wọ́n á sì fi tún ilé Jèhófà ṣe. 15 Wọn kì í sọ pé kí àwọn ọkùnrin náà ṣe ìṣirò owó tí wọ́n ní kí wọ́n fún àwọn òṣìṣẹ́, torí pé wọ́n ṣeé fọkàn tán.+ 16 Àmọ́ ṣá o, wọn kì í mú owó ẹbọ ẹ̀bi+ àti owó ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ wá sí ilé Jèhófà; ti àwọn àlùfáà ni.+
17 Ìgbà náà ni Hásáẹ́lì+ ọba Síríà lọ bá Gátì+ jà, ó sì gbà á, lẹ́yìn náà ó pinnu láti gbéjà ko Jerúsálẹ́mù.*+ 18 Ni Jèhóáṣì ọba Júdà bá kó gbogbo ọrẹ mímọ́ tí Jèhóṣáfátì, Jèhórámù àti Ahasáyà, àwọn baba ńlá rẹ̀, àwọn ọba Júdà, ti yà sí mímọ́ àti àwọn ọrẹ mímọ́ tirẹ̀ àti gbogbo wúrà tí wọ́n rí ní àwọn ibi ìṣúra ilé Jèhófà àti ilé* ọba, ó sì kó wọn ránṣẹ́ sí Hásáẹ́lì ọba Síríà.+ Nítorí náà, ó fi Jerúsálẹ́mù sílẹ̀.
19 Ní ti ìyókù ìtàn Jèhóáṣì àti gbogbo ohun tí ó ṣe, ǹjẹ́ kò wà lákọsílẹ̀ nínú ìwé ìtàn ìgbà àwọn ọba Júdà? 20 Àmọ́, àwọn ìránṣẹ́ Jèhóáṣì dìtẹ̀ mọ́ ọn,+ wọ́n sì pa á ní ilé Òkìtì,*+ ní ọ̀nà tó lọ sí Síílà. 21 Àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀, Jósákà ọmọ Ṣíméátì àti Jèhósábádì ọmọ Ṣómà, ló ṣá a balẹ̀, tí wọ́n sì pa á.+ Wọ́n sin ín pẹ̀lú àwọn baba ńlá rẹ̀ sí Ìlú Dáfídì, Amasááyà ọmọ rẹ̀ sì jọba ní ipò rẹ̀.+
13 Ní ọdún kẹtàlélógún Jèhóáṣì+ ọmọ Ahasáyà+ ọba Júdà, Jèhóáhásì ọmọ Jéhù+ di ọba lórí Ísírẹ́lì ní Samáríà, ọdún mẹ́tàdínlógún (17) ló sì fi ṣàkóso. 2 Ó ń ṣe ohun tó burú lójú Jèhófà, kò sì jáwọ́ nínú ẹ̀ṣẹ̀ tí Jèróbóámù ọmọ Nébátì mú kí Ísírẹ́lì dá.+ Kò ṣíwọ́ nínú rẹ̀. 3 Torí náà, ìbínú Jèhófà+ ru sí Ísírẹ́lì,+ ó sì fi wọ́n lé ọwọ́ Hásáẹ́lì+ ọba Síríà àti Bẹni-hádádì+ ọmọ Hásáẹ́lì ní gbogbo ìgbà náà.
4 Nígbà tó yá, Jèhóáhásì bẹ Jèhófà fún ojú rere,* Jèhófà sì gbọ́ ẹ̀bẹ̀ rẹ̀ torí pé ó ti rí ìnira tí ọba Síríà mú bá Ísírẹ́lì.+ 5 Jèhófà wá fún Ísírẹ́lì ní olùgbàlà+ kan tó máa gbà wọ́n lọ́wọ́ Síríà, èyí sì mú kó ṣeé ṣe fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì láti máa gbé nínú ilé wọn bíi ti tẹ́lẹ̀.* 6 (Síbẹ̀, wọn kò jáwọ́ nínú ẹ̀ṣẹ̀ tí ilé Jèróbóámù mú kí Ísírẹ́lì dá.+ Wọ́n ń dá ẹ̀ṣẹ̀ yìí nìṣó,* òpó òrìṣà*+ ṣì wà ní ìdúró ní Samáríà.) 7 Àádọ́ta (50) agẹṣin àti kẹ̀kẹ́ ẹṣin mẹ́wàá pẹ̀lú ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá (10,000) ọmọ ogun tó ń fẹsẹ̀ rìn ló ṣẹ́ kù fún Jèhóáhásì, torí pé ọba Síríà ti run wọ́n,+ ó sì tẹ̀ wọ́n rẹ́ bí erùpẹ̀ ibi ìpakà.+
8 Ní ti ìyókù ìtàn Jèhóáhásì àti gbogbo ohun tí ó ṣe àti agbára rẹ̀, ǹjẹ́ kò wà lákọsílẹ̀ nínú ìwé ìtàn ìgbà àwọn ọba Ísírẹ́lì? 9 Níkẹyìn, Jèhóáhásì sinmi pẹ̀lú àwọn baba ńlá rẹ̀, wọ́n sì sin ín sí Samáríà;+ Jèhóáṣì ọmọ rẹ̀ sì jọba ní ipò rẹ̀.
10 Ní ọdún kẹtàdínlógójì Jèhóáṣì ọba Júdà, Jèhóáṣì+ ọmọ Jèhóáhásì di ọba lórí Ísírẹ́lì ní Samáríà, ọdún mẹ́rìndínlógún (16) ni ó sì fi ṣàkóso. 11 Ó ń ṣe ohun tó burú lójú Jèhófà, kò jáwọ́ nínú gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ tí Jèróbóámù ọmọ Nébátì mú kí Ísírẹ́lì dá.+ Ó ń dá àwọn ẹ̀ṣẹ̀ náà nìṣó.*
12 Ní ti ìtàn Jèhóáṣì àti gbogbo ohun tí ó ṣe àti agbára rẹ̀ àti bí ó ṣe bá Amasááyà ọba Júdà+ jà, ǹjẹ́ kò wà lákọsílẹ̀ nínú ìwé ìtàn ìgbà àwọn ọba Ísírẹ́lì? 13 Níkẹyìn, Jèhóáṣì sinmi pẹ̀lú àwọn baba ńlá rẹ̀, Jèróbóámù*+ wá jókòó sórí ìtẹ́ rẹ̀. Wọ́n sì sin Jèhóáṣì sí Samáríà pẹ̀lú àwọn ọba Ísírẹ́lì.+
14 Nígbà tí ara Èlíṣà+ kò yá, tó sì jẹ́ pé àìsàn tó ń ṣe é yìí ló máa yọrí sí ikú rẹ̀, Jèhóáṣì ọba Ísírẹ́lì wá bá a, ó sì ń sunkún bó ṣe gbá a mọ́ra, ó sọ pé: “Bàbá mi, bàbá mi! Kẹ̀kẹ́ ẹṣin Ísírẹ́lì àti àwọn agẹṣin rẹ̀!”+ 15 Èlíṣà bá sọ fún un pé: “Mú ọrun àti àwọn ọfà.” Torí náà, ó mú ọrun àti àwọn ọfà. 16 Lẹ́yìn náà, ó sọ fún ọba Ísírẹ́lì pé: “Fi ọwọ́ rẹ di ọrun náà mú.” Torí náà, ó dì í mú, lẹ́yìn náà Èlíṣà gbé ọwọ́ lé ọwọ́ ọba. 17 Ó wá sọ pé: “Ṣí fèrèsé* tó dojú kọ ìlà oòrùn.” Torí náà, ó ṣí i. Èlíṣà sọ pé: “Ta á!” Nítorí náà, ó ta á. Ló bá sọ pé: “Ọfà ìṣẹ́gun* Jèhófà, ọfà ìṣẹ́gun* lórí Síríà! Wàá ṣá Síríà balẹ̀* ní Áfékì+ títí wàá fi pa á run.”
18 Ó ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ pé: “Kó àwọn ọfà náà,” ó sì kó wọn. Lẹ́yìn náà, ó sọ fún ọba Ísírẹ́lì pé: “Fi wọ́n na ilẹ̀.” Nítorí náà, ó fi wọ́n na ilẹ̀ lẹ́ẹ̀mẹta, ló bá dáwọ́ dúró. 19 Ni èèyàn Ọlọ́run tòótọ́ bá bínú sí i, ó sì sọ pé: “Ẹ̀ẹ̀márùn-ún tàbí ẹ̀ẹ̀mẹ́fà ló yẹ kí o fi wọ́n na ilẹ̀! Ká ní o ṣe bẹ́ẹ̀ ni, ì bá ṣeé ṣe fún ọ láti ṣá Síríà balẹ̀ títí wàá fi pa á run, àmọ́ ní báyìí, ẹ̀ẹ̀mẹ́ta péré lo máa ṣá Síríà balẹ̀.”+
20 Lẹ́yìn ìyẹn, Èlíṣà kú, wọ́n sì sin ín. Àwọn jàǹdùkú* ará Móábù+ máa ń wá sí ilẹ̀ náà ní ìbẹ̀rẹ̀ ọdún.* 21 Lọ́jọ́ kan, bí àwọn kan ṣe fẹ́ máa sin òkú ọkùnrin kan, wọ́n rí àwọn jàǹdùkú* náà, wọ́n bá sáré ju òkú ọkùnrin náà sínú ibojì Èlíṣà, wọ́n sì sá lọ. Nígbà tí òkú ọkùnrin náà fara kan egungun Èlíṣà, ó jí dìde,+ ó sì dìde dúró.
22 Hásáẹ́lì+ ọba Síríà ń ni Ísírẹ́lì lára+ ní gbogbo ọjọ́ Jèhóáhásì. 23 Àmọ́, Jèhófà ṣíjú àánú wò wọ́n, ó ṣojú rere sí wọn,+ ó sì bójú tó wọn nítorí májẹ̀mú rẹ̀ pẹ̀lú Ábúráhámù,+ Ísákì+ àti Jékọ́bù.+ Kò fẹ́ pa wọ́n run, kò sì ta wọ́n nù kúrò níwájú rẹ̀ títí di òní yìí. 24 Nígbà tí Hásáẹ́lì ọba Síríà kú, Bẹni-hádádì ọmọ rẹ̀ jọba ní ipò rẹ̀. 25 Nígbà náà, Jèhóáṣì ọmọ Jèhóáhásì gba àwọn ìlú pa dà lọ́wọ́ Bẹni-hádádì ọmọ Hásáẹ́lì, ìyẹn àwọn ìlú tí Hásáẹ́lì gbà lọ́wọ́ Jèhóáhásì bàbá rẹ̀ lójú ogun. Ẹ̀ẹ̀mẹ́ta ni Jèhóáṣì ṣá a balẹ̀,*+ ó sì gba àwọn ìlú Ísírẹ́lì pa dà.
14 Ní ọdún kejì Jèhóáṣì+ ọmọ Jèhóáhásì ọba Ísírẹ́lì, Amasááyà ọmọ Jèhóáṣì ọba Júdà di ọba. 2 Ẹni ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n (25) ni nígbà tó jọba, ọdún mọ́kàndínlọ́gbọ̀n (29) ló sì fi ṣàkóso ní Jerúsálẹ́mù. Orúkọ ìyá rẹ̀ ni Jèhóádínì láti Jerúsálẹ́mù.+ 3 Ó ń ṣe ohun tí ó tọ́ ní ojú Jèhófà, àmọ́ kì í ṣe bíi ti Dáfídì+ baba ńlá rẹ̀. Gbogbo ohun tí Jèhóáṣì bàbá rẹ̀ ṣe ni òun náà ṣe.+ 4 Àmọ́ kò mú àwọn ibi gíga kúrò,+ àwọn èèyàn náà ṣì ń rúbọ, wọ́n sì ń mú ẹbọ rú èéfín ní àwọn ibi gíga.+ 5 Nígbà tí ìjọba rẹ̀ ti fìdí múlẹ̀ dáadáa, ó pa àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ tí wọ́n pa bàbá rẹ̀ ọba.+ 6 Àmọ́ kò pa ọmọ àwọn apààyàn náà, gẹ́gẹ́ bí àṣẹ Jèhófà tó wà lákọsílẹ̀ nínú ìwé Òfin Mósè, pé: “Kí a má pa àwọn bàbá nítorí àwọn ọmọ wọn, kí a má sì pa àwọn ọmọ nítorí àwọn bàbá wọn; ṣùgbọ́n kí a pa kálukú nítorí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀.”+ 7 Ó pa àwọn ọmọ Édómù+ ní Àfonífojì Iyọ̀,+ ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá (10,000) èèyàn ló kú, ó sì gba ìlú Sẹ́ẹ́là lójú ogun,+ orúkọ ìlú náà sì di Jókítéélì títí di òní yìí.
8 Nígbà náà, Amasááyà rán àwọn òjíṣẹ́ sí Jèhóáṣì ọmọ Jèhóáhásì ọmọ Jéhù ọba Ísírẹ́lì pé: “Wá, jẹ́ ká dojú ìjà kọ ara wa.”*+ 9 Jèhóáṣì ọba Ísírẹ́lì ránṣẹ́ sí Amasááyà ọba Júdà, pé: “Èpò ẹlẹ́gùn-ún tó wà ní Lẹ́bánónì ránṣẹ́ sí igi kédárì tó wà ní Lẹ́bánónì, pé, ‘Fi ọmọbìnrin rẹ fún ọmọkùnrin mi kó fi ṣe aya.’ Àmọ́, ẹranko kan láti Lẹ́bánónì kọjá, ó sì tẹ èpò ẹlẹ́gùn-ún náà pa. 10 Òótọ́ ni pé o ti ṣẹ́gun Édómù,+ torí bẹ́ẹ̀ ni ìgbéraga fi wọ̀ ẹ́ lẹ́wù. Dúró sí ilé* rẹ, kí o sì jẹ́ kí ògo rẹ máa múnú rẹ dùn. Kí ló dé tí wàá fi fa àjálù bá ara rẹ, tí wàá sì gbé ara rẹ àti Júdà ṣubú?” 11 Ṣùgbọ́n Amasááyà ò gbọ́.+
Torí náà, Jèhóáṣì ọba Ísírẹ́lì jáde lọ, òun àti Amasááyà ọba Júdà sì dojú ìjà kọra ní Bẹti-ṣémẹ́ṣì,+ tó jẹ́ ti Júdà.+ 12 Ísírẹ́lì ṣẹ́gun Júdà, kálukú sì sá lọ sí ilé* rẹ̀. 13 Jèhóáṣì ọba Ísírẹ́lì mú Amasááyà ọba Júdà, ọmọ Jèhóáṣì ọmọ Ahasáyà, ní Bẹti-ṣémẹ́ṣì. Lẹ́yìn náà, wọ́n wá sí Jerúsálẹ́mù, ó sì ṣe àlàfo sára ògiri Jerúsálẹ́mù láti Ẹnubodè Éfúrémù+ títí dé Ẹnubodè Igun,+ ọgọ́rùn-ún mẹ́rin (400) ìgbọ̀nwọ́.* 14 Ó kó gbogbo wúrà àti fàdákà pẹ̀lú gbogbo ohun èlò tó wà ní ilé Jèhófà àti ní àwọn ibi tí wọ́n ń kó ìṣúra sí ní ilé* ọba àti àwọn tí wọ́n mú lóǹdè. Lẹ́yìn náà, ó pa dà sí Samáríà.
15 Ní ti ìyókù ìtàn Jèhóáṣì, ohun tí ó ṣe àti agbára rẹ̀ àti bí ó ṣe bá Amasááyà ọba Júdà jà, ǹjẹ́ kò wà lákọsílẹ̀ nínú ìwé ìtàn ìgbà àwọn ọba Ísírẹ́lì? 16 Níkẹyìn, Jèhóáṣì sinmi pẹ̀lú àwọn baba ńlá rẹ̀, wọ́n sì sin ín sí Samáríà+ pẹ̀lú àwọn ọba Ísírẹ́lì; Jèróbóámù*+ ọmọ rẹ̀ sì jọba ní ipò rẹ̀.
17 Amasááyà+ ọmọ Jèhóáṣì ọba Júdà lo ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún (15) sí i lẹ́yìn ikú Jèhóáṣì+ ọmọ Jèhóáhásì ọba Ísírẹ́lì.+ 18 Ní ti ìyókù ìtàn Amasááyà, ǹjẹ́ kò wà lákọsílẹ̀ nínú ìwé ìtàn ìgbà àwọn ọba Júdà? 19 Nígbà tó yá, àwọn kan dìtẹ̀ mọ́ ọn+ ní Jerúsálẹ́mù, ó sì sá lọ sí Lákíṣì, àmọ́ wọ́n rán àwọn kan tẹ̀ lé e lọ sí Lákíṣì, wọ́n sì pa á síbẹ̀. 20 Nítorí náà, wọ́n fi ẹṣin gbé e pa dà, wọ́n sì sin ín sí Jerúsálẹ́mù pẹ̀lú àwọn baba ńlá rẹ̀ ní Ìlú Dáfídì.+ 21 Lẹ́yìn náà, gbogbo àwọn èèyàn Júdà mú Asaráyà*+ tó jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́rìndínlógún (16),+ wọ́n sì fi í jọba ní ipò Amasááyà bàbá rẹ̀.+ 22 Ó tún Élátì+ kọ́, ó sì dá a pa dà fún Júdà lẹ́yìn tí ọba* ti sinmi pẹ̀lú àwọn baba ńlá rẹ̀.+
23 Ní ọdún kẹẹ̀ẹ́dógún Amasááyà ọmọ Jèhóáṣì ọba Júdà, Jèróbóámù+ ọmọ Jèhóáṣì ọba Ísírẹ́lì di ọba ní Samáríà, ọdún mọ́kànlélógójì (41) ló sì fi ṣàkóso. 24 Ó ń ṣe ohun tó burú ní ojú Jèhófà. Kò jáwọ́ nínú gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ tí Jèróbóámù ọmọ Nébátì mú kí Ísírẹ́lì dá.+ 25 Ó gba ààlà ilẹ̀ Ísírẹ́lì pa dà láti Lebo-hámátì*+ títí dé Òkun Árábà,*+ gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ tí Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì gbẹnu ìránṣẹ́ rẹ̀ sọ, ìyẹn Jónà+ ọmọ Ámítáì, wòlíì tó wá láti Gati-héférì.+ 26 Nítorí Jèhófà ti rí i pé ìpọ́njú tó bá Ísírẹ́lì pọ̀ gan-an.+ Kò sẹ́ni tó ṣẹ́ kù tó lè ran Ísírẹ́lì lọ́wọ́, títí kan àwọn aláìní tàbí àwọn aláìlera. 27 Àmọ́ Jèhófà ti ṣèlérí pé òun kò ní pa orúkọ Ísírẹ́lì rẹ́ kúrò lábẹ́ ọ̀run.+ Torí náà, ó lo Jèróbóámù ọmọ Jèhóáṣì láti gbà wọ́n.+
28 Ní ti ìyókù ìtàn Jèróbóámù àti gbogbo ohun tí ó ṣe àti agbára rẹ̀, bí ó ṣe jà àti bí ó ṣe gba Damásíkù+ àti Hámátì+ pa dà fún Júdà ní Ísírẹ́lì, ǹjẹ́ kò wà lákọsílẹ̀ nínú ìwé ìtàn ìgbà àwọn ọba Ísírẹ́lì? 29 Níkẹyìn, Jèróbóámù sinmi pẹ̀lú àwọn baba ńlá rẹ̀, àwọn ọba Ísírẹ́lì; Sekaráyà+ ọmọ rẹ̀ sì jọba ní ipò rẹ̀.
15 Ní ọdún kẹtàdínlọ́gbọ̀n Jèróbóámù* ọba Ísírẹ́lì, Asaráyà*+ ọmọ Amasááyà+ ọba Júdà di ọba.+ 2 Ọmọ ọdún mẹ́rìndínlógún (16) ni nígbà tó jọba, ọdún méjìléláàádọ́ta (52) ló sì fi ṣàkóso ní Jerúsálẹ́mù. Orúkọ ìyá rẹ̀ ni Jekoláyà tó wá láti Jerúsálẹ́mù. 3 Ó ń ṣe ohun tí ó tọ́ ní ojú Jèhófà bí Amasááyà bàbá rẹ̀ ti ṣe.+ 4 Àmọ́ kò mú àwọn ibi gíga kúrò,+ àwọn èèyàn náà ṣì ń rúbọ, wọ́n sì ń mú ẹbọ rú èéfín ní àwọn ibi gíga.+ 5 Jèhófà fi àrùn kọ lu ọba, ó sì ya adẹ́tẹ̀+ títí di ọjọ́ ikú rẹ̀; inú ilé kan tó wà lọ́tọ̀ ló ń gbé,+ lásìkò yìí Jótámù+ ọmọ ọba ló ń bójú tó ilé,* ó sì ń dá ẹjọ́ àwọn èèyàn ilẹ̀ náà.+ 6 Ní ti ìyókù ìtàn Asaráyà+ àti gbogbo ohun tí ó ṣe, ǹjẹ́ kò wà lákọsílẹ̀ nínú ìwé ìtàn ìgbà àwọn ọba Júdà? 7 Níkẹyìn, Asaráyà sinmi pẹ̀lú àwọn baba ńlá rẹ̀,+ wọ́n sì sin ín pẹ̀lú àwọn baba ńlá rẹ̀ ní Ìlú Dáfídì; Jótámù ọmọ rẹ̀ sì jọba ní ipò rẹ̀.
8 Ní ọdún kejìdínlógójì Asaráyà+ ọba Júdà, Sekaráyà+ ọmọ Jèróbóámù di ọba lórí Ísírẹ́lì ní Samáríà, ó sì fi oṣù mẹ́fà ṣàkóso. 9 Ó ṣe ohun tó burú lójú Jèhófà bí àwọn baba ńlá rẹ̀ ti ṣe. Kò jáwọ́ nínú àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tí Jèróbóámù ọmọ Nébátì mú kí Ísírẹ́lì dá.+ 10 Ìgbà náà ni Ṣálúmù ọmọ Jábéṣì dìtẹ̀ mọ́ ọn, ó sì pa á+ ní Íbíléámù.+ Lẹ́yìn tó pa á, ó jọba ní ipò rẹ̀. 11 Ní ti ìyókù ìtàn Sekaráyà, ó wà lákọsílẹ̀ nínú ìwé ìtàn ìgbà àwọn ọba Ísírẹ́lì. 12 Èyí mú kí ọ̀rọ̀ tí Jèhófà sọ fún Jéhù ṣẹ pé: “Àwọn ọmọ rẹ títí dé ìran kẹrin+ yóò máa jókòó lórí ìtẹ́ Ísírẹ́lì.”+ Bó sì ṣe ṣẹlẹ̀ nìyẹn.
13 Ṣálúmù ọmọ Jábéṣì di ọba ní ọdún kọkàndínlógójì Ùsáyà+ ọba Júdà, oṣù kan ló sì fi ṣàkóso ní Samáríà. 14 Ìgbà náà ni Ménáhémù ọmọ Gádì wá láti Tírísà+ sí Samáríà, ó sì pa Ṣálúmù+ ọmọ Jábéṣì ní Samáríà. Lẹ́yìn tó pa á, ó jọba ní ipò rẹ̀. 15 Ní ti ìyókù ìtàn Ṣálúmù àti ọ̀tẹ̀ tó dì, ó wà lákọsílẹ̀ nínú ìwé ìtàn ìgbà àwọn ọba Ísírẹ́lì. 16 Ìgbà náà ni Ménáhémù wá láti Tírísà, ó sì ṣẹ́gun Tífísà àti gbogbo àwọn tó wà nínú rẹ̀ àti ìpínlẹ̀ rẹ̀, nítorí pé wọn kò ṣí ẹnubodè rẹ̀ fún un. Ó pa ìlú náà run, ó sì la inú àwọn aboyún tó wà níbẹ̀.
17 Ní ọdún kọkàndínlógójì Asaráyà ọba Júdà, Ménáhémù ọmọ Gádì di ọba lórí Ísírẹ́lì, ó sì fi ọdún mẹ́wàá ṣàkóso ní Samáríà. 18 Ó ń ṣe ohun tó burú lójú Jèhófà. Kò jáwọ́ nínú gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ tí Jèróbóámù ọmọ Nébátì mú kí Ísírẹ́lì dá,+ ní gbogbo ọjọ́ rẹ̀. 19 Púlì+ ọba Ásíríà wá sí ilẹ̀ náà, Ménáhémù sì fún Púlì ní ẹgbẹ̀rún kan (1,000) tálẹ́ńtì* fàdákà nítorí ó tì í lẹ́yìn kí ìjọba má bàa bọ́ mọ́ ọn lọ́wọ́.+ 20 Nítorí náà, Ménáhémù gba fàdákà náà jọ ní Ísírẹ́lì látọwọ́ àwọn ọlọ́rọ̀ tó lókìkí.+ Ó fún ọba Ásíríà ní àádọ́ta (50) ṣékélì* fàdákà lórí ọkùnrin kọ̀ọ̀kan. Ni ọba Ásíríà bá yíjú pa dà, kò sì dúró ní ilẹ̀ náà. 21 Ní ti ìyókù ìtàn Ménáhémù+ àti gbogbo ohun tí ó ṣe, ǹjẹ́ kò wà lákọsílẹ̀ nínú ìwé ìtàn ìgbà àwọn ọba Ísírẹ́lì? 22 Níkẹyìn, Ménáhémù sinmi pẹ̀lú àwọn baba ńlá rẹ̀; Pekaháyà ọmọ rẹ̀ sì jọba ní ipò rẹ̀.
23 Ní àádọ́ta ọdún Asaráyà ọba Júdà, Pekaháyà ọmọ Ménáhémù di ọba lórí Ísírẹ́lì ní Samáríà, ọdún méjì ló sì fi ṣàkóso. 24 Ó ń ṣe ohun tó burú ní ojú Jèhófà. Kò jáwọ́ nínú àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tí Jèróbóámù ọmọ Nébátì mú kí Ísírẹ́lì dá.+ 25 Lẹ́yìn náà, olùrànlọ́wọ́ rẹ̀ lójú ogun, ìyẹn Pékà+ ọmọ Remaláyà dìtẹ̀ mọ́ ọn, ó sì pa á ní Samáríà nínú ilé gogoro tó láàbò tó wà ní ilé* ọba, pẹ̀lú Ágóbù àti Áríè. Àádọ́ta (50) ọkùnrin láti ilẹ̀ Gílíádì sì wà pẹ̀lú rẹ̀; lẹ́yìn tó pa á, ó jọba ní ipò rẹ̀. 26 Ní ti ìyókù ìtàn Pekaháyà àti gbogbo ohun tí ó ṣe, ó wà lákọsílẹ̀ nínú ìwé ìtàn ìgbà àwọn ọba Ísírẹ́lì.
27 Ní ọdún kejìléláàádọ́ta Asaráyà ọba Júdà, Pékà+ ọmọ Remaláyà di ọba lórí Ísírẹ́lì ní Samáríà, ogún (20) ọdún ló sì fi ṣàkóso. 28 Ó ń ṣe ohun tó burú ní ojú Jèhófà. Kò sì jáwọ́ nínú àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tí Jèróbóámù ọmọ Nébátì mú kí Ísírẹ́lì dá.+ 29 Nígbà ayé Pékà ọba Ísírẹ́lì, Tigilati-pílésà+ ọba Ásíríà kógun wọ Íjónì, Ebẹli-bẹti-máákà,+ Jánóà, Kédéṣì,+ Hásórì, Gílíádì+ àti Gálílì, ìyẹn gbogbo ilẹ̀ Náfútálì,+ ó sì gbà á, ó wá kó àwọn tó ń gbé ibẹ̀ lọ sí ìgbèkùn ní Ásíríà.+ 30 Lẹ́yìn náà, Hóṣéà+ ọmọ Élà dìtẹ̀ mọ́ Pékà ọmọ Remaláyà, ó ṣá a balẹ̀, ó sì pa á; ó jọba ní ipò rẹ̀ ní ogún ọdún Jótámù+ ọmọ Ùsáyà. 31 Ní ti ìyókù ìtàn Pékà àti gbogbo ohun tí ó ṣe, ó wà lákọsílẹ̀ nínú ìwé ìtàn ìgbà àwọn ọba Ísírẹ́lì.
32 Ní ọdún kejì Pékà ọmọ Remaláyà ọba Ísírẹ́lì, Jótámù+ ọmọ Ùsáyà+ ọba Júdà jọba. 33 Ẹni ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n (25) ni nígbà tó jọba, ọdún mẹ́rìndínlógún (16) ló sì fi ṣàkóso ní Jerúsálẹ́mù. Orúkọ ìyá rẹ̀ ni Jẹ́rúṣà ọmọ Sádókù.+ 34 Ó ń ṣe ohun tí ó tọ́ lójú Jèhófà bí Ùsáyà bàbá rẹ̀ ti ṣe.+ 35 Àmọ́ kò mú àwọn ibi gíga kúrò, àwọn èèyàn náà ṣì ń rúbọ, wọ́n sì ń mú ẹbọ rú èéfín ní àwọn ibi gíga.+ Òun ló kọ́ ẹnubodè apá òkè tó wà ní ilé Jèhófà.+ 36 Ní ti ìyókù ìtàn Jótámù, ohun tí ó ṣe, ǹjẹ́ kò wà lákọsílẹ̀ nínú ìwé ìtàn ìgbà àwọn ọba Júdà? 37 Lákòókò yẹn, Jèhófà bẹ̀rẹ̀ sí í rán Résínì ọba Síríà àti Pékà+ ọmọ Remaláyà láti gbógun ti Júdà.+ 38 Níkẹyìn, Jótámù sinmi pẹ̀lú àwọn baba ńlá rẹ̀, wọ́n sì sin ín pẹ̀lú àwọn baba ńlá rẹ̀ sí Ìlú Dáfídì baba ńlá rẹ̀. Áhásì ọmọ rẹ̀ sì jọba ní ipò rẹ̀.
16 Ní ọdún kẹtàdínlógún Pékà ọmọ Remaláyà, Áhásì+ ọmọ Jótámù ọba Júdà di ọba. 2 Ẹni ogún (20) ọdún ni Áhásì nígbà tó jọba, ọdún mẹ́rìndínlógún (16) ló sì fi ṣàkóso ní Jerúsálẹ́mù. Kò ṣe ohun tí ó tọ́ ní ojú Jèhófà Ọlọ́run rẹ̀ bí Dáfídì baba ńlá rẹ̀ ti ṣe.+ 3 Kàkà bẹ́ẹ̀, ó rìn ní ọ̀nà àwọn ọba Ísírẹ́lì,+ kódà ó sun ọmọ rẹ̀ nínú iná,+ ó tipa bẹ́ẹ̀ ṣe ohun ìríra tí àwọn orílẹ̀-èdè+ tí Jèhófà lé kúrò níwájú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ń ṣe. 4 Ó tún ń rúbọ, ó sì ń mú ẹbọ rú èéfín lórí àwọn ibi gíga,+ lórí àwọn òkè àti lábẹ́ gbogbo igi tó gbẹ̀rẹ̀gẹ̀jigẹ̀.+
5 Ìgbà náà ni Résínì ọba Síríà àti Pékà ọmọ Remaláyà ọba Ísírẹ́lì wá gbógun ja Jerúsálẹ́mù.+ Wọ́n dó ti Áhásì, àmọ́ wọn ò rí ìlú náà gbà. 6 Ní àkókò yẹn, Résínì ọba Síríà gba Élátì + pa dà fún Édómù, lẹ́yìn náà, ó lé àwọn Júù* kúrò ní Élátì. Àwọn ọmọ Édómù wọ Élátì, wọ́n sì ń gbé ibẹ̀ títí di òní yìí. 7 Nítorí náà, Áhásì rán àwọn òjíṣẹ́ sí Tigilati-pílésà+ ọba Ásíríà, ó ní: “Ìránṣẹ́ rẹ ni mí, ọmọ rẹ sì ni mo jẹ́. Wá gbà mí lọ́wọ́ ọba Síríà àti lọ́wọ́ ọba Ísírẹ́lì tí wọ́n ń gbéjà kò mí.” 8 Áhásì wá kó fàdákà àti wúrà tí wọ́n rí ní ilé Jèhófà àti ní àwọn ibi ìṣúra ilé* ọba, ó sì fi àbẹ̀tẹ́lẹ̀ ránṣẹ́ sí ọba Ásíríà.+ 9 Ọba Ásíríà gbọ́ ẹ̀bẹ̀ rẹ̀, ó lọ sí Damásíkù, ó sì gbà á, ó kó àwọn èèyàn inú rẹ̀ lọ sí ìgbèkùn ní Kírì,+ ó sì pa Résínì.+
10 Lẹ́yìn náà, Ọba Áhásì lọ pàdé Tigilati-pílésà ọba Ásíríà ní Damásíkù. Nígbà tó rí pẹpẹ tó wà ní Damásíkù, Ọba Áhásì fi àwòrán pẹpẹ náà ránṣẹ́ sí àlùfáà Úríjà, iṣẹ́ ọnà pẹpẹ náà àti bí wọ́n ṣe mọ ọ́n ló wà nínú àwòrán náà.+ 11 Àlùfáà Úríjà+ mọ pẹpẹ+ kan gẹ́gẹ́ bí gbogbo ìlànà tí Ọba Áhásì fi ránṣẹ́ láti Damásíkù. Àlùfáà Úríjà parí mímọ pẹpẹ náà kí Ọba Áhásì tó dé láti Damásíkù. 12 Nígbà tí ọba dé láti Damásíkù tó sì rí pẹpẹ náà, ó lọ sídìí rẹ̀, ó sì rú àwọn ẹbọ lórí rẹ̀.+ 13 Orí pẹpẹ náà ló ti mú àwọn ẹbọ sísun rẹ̀ àti àwọn ọrẹ ọkà rẹ̀ rú èéfín; ó tún da àwọn ọrẹ ohun mímu rẹ̀ jáde, ó sì wọ́n ẹ̀jẹ̀ àwọn ẹbọ ìrẹ́pọ̀ rẹ̀ sórí pẹpẹ náà. 14 Nígbà náà, ó gbé pẹpẹ bàbà+ tó wà níwájú Jèhófà kúrò ní àyè rẹ̀ níwájú ilé náà, ìyẹn láti àárín pẹpẹ rẹ̀ àti ilé Jèhófà, ó sì gbé e sí apá àríwá pẹpẹ rẹ̀. 15 Ọba Áhásì pàṣẹ fún àlùfáà Úríjà+ pé: “Mú ẹbọ sísun àárọ̀ rú èéfín lórí pẹpẹ ńlá,+ ohun kan náà ni kí o ṣe sí ọrẹ ọkà ìrọ̀lẹ́,+ ẹbọ sísun ọba àti ọrẹ ọkà rẹ̀, títí kan àwọn ẹbọ sísun gbogbo àwọn èèyàn náà, àwọn ọrẹ ọkà wọn àti àwọn ọrẹ ohun mímu wọn. Kí o wọ́n gbogbo ẹ̀jẹ̀ àwọn ẹbọ sísun àti gbogbo ẹ̀jẹ̀ àwọn ẹbọ yòókù sórí rẹ̀. Ní ti pẹpẹ bàbà náà, jẹ́ kí n pinnu ohun tí màá ṣe nípa rẹ̀.” 16 Àlùfáà Úríjà ṣe gbogbo ohun tí Ọba Áhásì pa láṣẹ.+
17 Yàtọ̀ síyẹn, Ọba Áhásì gé àwọn iṣẹ́ ọnà pẹlẹbẹ-pẹlẹbẹ+ tó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ àwọn kẹ̀kẹ́ ẹrù sí wẹ́wẹ́, ó sì gbé bàsíà kúrò lórí àwọn kẹ̀kẹ́ ẹrù náà,+ ó sọ Òkun kalẹ̀ lórí àwọn akọ màlúù+ tó gbé e dúró, ó sì gbé e sórí ibi tí a fi òkúta tẹ́.+ 18 Ibi tó ní ìbòrí tí wọ́n ń lò ní Sábáàtì, èyí tí wọ́n kọ́ sí ilé náà àti ọ̀nà àbáwọlé ọba tó wà ní ìta ló gbé kúrò ní ilé Jèhófà lọ sí ibòmíì; ó ṣe bẹ́ẹ̀ nítorí ọba Ásíríà.
19 Ní ti ìyókù ìtàn Áhásì, ohun tí ó ṣe, ǹjẹ́ kò wà lákọsílẹ̀ nínú ìwé ìtàn ìgbà àwọn ọba Júdà?+ 20 Níkẹyìn, Áhásì sinmi pẹ̀lú àwọn baba ńlá rẹ̀, wọ́n sì sin ín pẹ̀lú àwọn baba ńlá rẹ̀ sí Ìlú Dáfídì; Hẹsikáyà*+ ọmọ rẹ̀ sì jọba ní ipò rẹ̀.
17 Ní ọdún kejìlá Áhásì ọba Júdà, Hóṣéà+ ọmọ Élà di ọba ní Samáríà lórí Ísírẹ́lì; ọdún mẹ́sàn-án ló sì fi ṣàkóso. 2 Ó ń ṣe ohun tó burú ní ojú Jèhófà, kìkì pé kò ṣe tó ti àwọn ọba Ísírẹ́lì tó ṣáájú rẹ̀. 3 Ṣálímánésà ọba Ásíríà wá gbéjà ko Hóṣéà,+ Hóṣéà sì di ìránṣẹ́ rẹ̀, ó wá bẹ̀rẹ̀ sí í san ìṣákọ́lẹ̀* fún Ṣálímánésà.+ 4 Àmọ́, ọba Ásíríà rí i pé Hóṣéà ti ń lọ́wọ́ nínú ọ̀tẹ̀, nítorí ó rán àwọn òjíṣẹ́ sí Sóò ọba Íjíbítì,+ kò sì mú ìṣákọ́lẹ̀* wá fún ọba Ásíríà bíi ti àwọn ọdún àtẹ̀yìnwá. Nítorí náà, ọba Ásíríà tì í mọ́ inú ẹ̀wọ̀n, ó sì fi ṣẹkẹ́ṣẹkẹ̀ dè é.
5 Ọba Ásíríà ya wọ gbogbo ilẹ̀ náà, ó wá sí Samáríà, ọdún mẹ́ta ló sì fi dó tì í. 6 Ní ọdún kẹsàn-án Hóṣéà, ọba Ásíríà gba Samáríà.+ Ó wá kó àwọn èèyàn Ísírẹ́lì ní ìgbèkùn+ lọ sí Ásíríà, ó sì mú kí wọ́n máa gbé ní Hálà àti ní Hábórì níbi odò Gósánì+ àti ní àwọn ìlú àwọn ará Mídíà.+
7 Ohun tó fa èyí ni pé àwọn èèyàn Ísírẹ́lì ṣẹ̀ sí Jèhófà Ọlọ́run wọn, ẹni tó mú wọn jáde kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì, kúrò lábẹ́ àṣẹ Fáráò ọba Íjíbítì.+ Wọ́n sin* àwọn ọlọ́run míì,+ 8 wọ́n tẹ̀ lé àṣà àwọn orílẹ̀-èdè tí Jèhófà lé kúrò níwájú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, wọ́n sì tẹ̀ lé àṣà tí àwọn ọba Ísírẹ́lì dá sílẹ̀.
9 Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ń ṣe àwọn nǹkan tí Jèhófà Ọlọ́run wọn sọ pé kò tọ́. Wọ́n ń kọ́ àwọn ibi gíga ní gbogbo àwọn ìlú wọn,+ láti ilé ìṣọ́ títí dé ìlú olódi.* 10 Wọ́n ń gbé àwọn ọwọ̀n òrìṣà àti àwọn òpó òrìṣà*+ kalẹ̀ fún ara wọn lórí gbogbo òkè àti lábẹ́ gbogbo igi tó gbẹ̀rẹ̀gẹ̀jigẹ̀;+ 11 orí gbogbo ibi gíga wọ̀nyí ni wọ́n ti ń mú ẹbọ rú èéfín bí àwọn orílẹ̀-èdè tí Jèhófà lé kúrò níwájú wọn lọ sí ìgbèkùn.+ Wọ́n ń fi ohun búburú tí wọ́n ṣe mú Jèhófà bínú.
12 Wọ́n ń sin àwọn òrìṣà ẹ̀gbin,*+ èyí tí Jèhófà sọ fún wọn pé: “Ẹ kò gbọ́dọ̀ ṣe nǹkan yìí!”+ 13 Jèhófà lo gbogbo wòlíì rẹ̀ àti gbogbo aríran+ rẹ̀ láti máa kìlọ̀ fún Ísírẹ́lì àti Júdà pé: “Ẹ kúrò nínú àwọn ọ̀nà búburú yín!+ Kí ẹ máa pa àwọn àṣẹ mi àti àwọn ìlànà mi mọ́, bó ṣe wà nínú gbogbo òfin tí mo pa láṣẹ fún àwọn baba ńlá yín, tí mo sì fi rán àwọn ìránṣẹ́ mi wòlíì sí yín.” 14 Àmọ́ wọn ò gbọ́, wọ́n sì ya alágídí bí* àwọn baba ńlá wọn tí kò ní ìgbàgbọ́ nínú Jèhófà Ọlọ́run wọn.+ 15 Wọ́n ń pa àwọn ìlànà rẹ̀ tì àti májẹ̀mú+ rẹ̀ tó bá àwọn baba ńlá wọn dá àti àwọn ìránnilétí rẹ̀ tó fi kìlọ̀ fún wọn,+ wọ́n ń sin àwọn òrìṣà asán,+ àwọn fúnra wọn sì di asán,+ torí wọ́n ń fara wé àwọn orílẹ̀-èdè tó yí wọn ká tí Jèhófà pàṣẹ fún wọn pé kí wọ́n má ṣe fara wé.+
16 Wọ́n ń pa gbogbo àṣẹ Jèhófà Ọlọ́run wọn tì, wọ́n sì ṣe ère onírin* ọmọ màlúù méjì,+ wọ́n ṣe òpó òrìṣà,*+ wọ́n ń forí balẹ̀ fún gbogbo ọmọ ogun ọ̀run,+ wọ́n sì ń sin Báálì.+ 17 Wọ́n tún ń sun àwọn ọmọkùnrin wọn àti àwọn ọmọbìnrin wọn nínú iná,+ wọ́n ń woṣẹ́,+ wọ́n ń wá àwọn àmì ìṣẹ̀lẹ̀, wọ́n pinnu* láti máa ṣe ohun tó burú ní ojú Jèhófà, wọ́n sì tipa bẹ́ẹ̀ mú un bínú.
18 Nítorí náà, inú bí Jèhófà gidigidi sí Ísírẹ́lì, tí ó fi mú wọn kúrò níwájú rẹ̀.+ Kò jẹ́ kí èyíkéyìí ṣẹ́ kù lára wọn àfi ẹ̀yà Júdà nìkan.
19 Àwọn èèyàn Júdà pàápàá kò pa àwọn àṣẹ Jèhófà Ọlọ́run wọn mọ́;+ àwọn náà ń tẹ̀ lé àṣà tí Ísírẹ́lì tẹ̀ lé.+ 20 Jèhófà kọ gbogbo àtọmọdọ́mọ Ísírẹ́lì sílẹ̀, ó dójú tì wọ́n, ó sì fi wọ́n lé ọwọ́ àwọn tó ń kóni lẹ́rù, títí ó fi lé wọn kúrò níwájú rẹ̀. 21 Ó fa Ísírẹ́lì ya kúrò ní ilé Dáfídì, wọ́n sì fi Jèróbóámù ọmọ Nébátì jọba.+ Àmọ́ Jèróbóámù mú kí Ísírẹ́lì yà kúrò lẹ́yìn Jèhófà, ó sì mú kí wọ́n dá ẹ̀ṣẹ̀ ńlá. 22 Àwọn èèyàn Ísírẹ́lì ń dá gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ tí Jèróbóámù dá.+ Wọn kò jáwọ́ nínú wọn 23 títí Jèhófà fi mú Ísírẹ́lì kúrò níwájú rẹ̀, bó ṣe sọ látẹnu gbogbo àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ wòlíì.+ Bí wọ́n ṣe kó Ísírẹ́lì nígbèkùn láti ilẹ̀ rẹ̀ lọ sí Ásíríà+ nìyẹn, wọ́n sì wà níbẹ̀ títí di òní yìí.
24 Lẹ́yìn náà, ọba Ásíríà kó àwọn èèyàn wá láti Bábílónì, Kútà, Áfà, Hámátì àti Séfáfáímù,+ ó sì ní kí wọ́n máa gbé inú àwọn ìlú Samáríà níbi tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ń gbé tẹ́lẹ̀; wọ́n gba Samáríà, wọ́n sì ń gbé inú àwọn ìlú rẹ̀. 25 Nígbà tí wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í gbé ibẹ̀, wọn kò bẹ̀rù* Jèhófà. Nítorí náà, Jèhófà rán àwọn kìnnìún sáàárín wọn,+ wọ́n sì pa lára àwọn èèyàn náà. 26 Wọ́n ròyìn fún ọba Ásíríà pé: “Àwọn orílẹ̀-èdè tí o kó lọ sí ìgbèkùn, tí o ní kí wọ́n máa gbé àwọn ìlú Samáríà kò mọ ẹ̀sìn* Ọlọ́run ilẹ̀ náà. Torí náà, ó ń rán àwọn kìnnìún sáàárín wọn, àwọn kìnnìún náà sì ń pa wọ́n, torí pé kò sí ìkankan nínú wọn tó mọ ẹ̀sìn Ọlọ́run ilẹ̀ náà.”
27 Ni ọba Ásíríà bá pàṣẹ pé: “Ẹ dá ọ̀kan lára àwọn àlùfáà tí ẹ kó láti ibẹ̀ lọ sí ìgbèkùn pa dà, kó lè máa gbé ibẹ̀, kó sì máa kọ́ wọn ní ẹ̀sìn Ọlọ́run ilẹ̀ náà.” 28 Torí náà, ọ̀kan lára àwọn àlùfáà tí wọ́n kó lọ sí ìgbèkùn láti Samáríà pa dà wá, ó sì ń gbé Bẹ́tẹ́lì,+ ó wá bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ wọn bí wọ́n á ṣe máa bẹ̀rù* Jèhófà.+
29 Àmọ́, orílẹ̀-èdè kọ̀ọ̀kan ṣe ọlọ́run tirẹ̀,* wọ́n gbé wọn sínú àwọn ilé ìjọsìn ní àwọn ibi gíga tí àwọn ará Samáríà ṣe; orílẹ̀-èdè kọ̀ọ̀kan ṣe bẹ́ẹ̀ ní ìlú wọn tí wọ́n ń gbé. 30 Àwọn èèyàn Bábílónì ṣe Sukotu-bénótì, àwọn èèyàn Kútì ṣe Nẹ́gálì, àwọn èèyàn Hámátì+ ṣe Áṣímà, 31 àwọn ará Áfà sì ṣe Níbúhásì àti Tátákì. Àwọn ará Séfáfáímù máa ń sun àwọn ọmọ wọn nínú iná sí Adiramélékì àti Anamélékì, àwọn ọlọ́run Séfáfáímù.+ 32 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n bẹ̀rù Jèhófà, wọ́n yan àwọn àlùfáà sí àwọn ibi gíga látinú àwọn èèyàn wọn, àwọn yìí ló ń bá wọn ṣiṣẹ́ ní àwọn ilé ìjọsìn ní àwọn ibi gíga.+ 33 Nípa bẹ́ẹ̀, wọ́n ń bẹ̀rù Jèhófà, àmọ́ àwọn ọlọ́run wọn ni wọ́n ń sìn bí wọ́n ti ń ṣe nínú ẹ̀sìn* àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n ti kó wọn wá.+
34 Títí di òní yìí, ẹ̀sìn* wọn àtẹ̀yìnwá ni wọ́n ń ṣe. Kò sí ìkankan lára wọn tó sin* Jèhófà, bẹ́ẹ̀ ni kò sí ìkankan lára wọn tó tẹ̀ lé ìlànà rẹ̀ àti ìdájọ́ rẹ̀, wọn ò sì pa Òfin àti àṣẹ tí Jèhófà fún àwọn ọmọ Jékọ́bù mọ́, ẹni tí Ó yí orúkọ rẹ̀ pa dà sí Ísírẹ́lì.+ 35 Nígbà tí Jèhófà bá wọn dá májẹ̀mú,+ ó pàṣẹ fún wọn pé: “Ẹ kò gbọ́dọ̀ bẹ̀rù àwọn ọlọ́run míì, ẹ kò sì gbọ́dọ̀ forí balẹ̀ fún wọn tàbí kí ẹ sìn wọ́n tàbí kí ẹ rúbọ sí wọn.+ 36 Ṣùgbọ́n Jèhófà, ẹni tó mú yín jáde kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì pẹ̀lú agbára ńlá àti apá tó nà jáde,+ ni Ẹni tí ẹ ó máa bẹ̀rù,+ òun ni kí ẹ máa forí balẹ̀ fún, òun sì ni kí ẹ máa rúbọ sí. 37 Àwọn ìlànà, àwọn ìdájọ́ àti Òfin pẹ̀lú àṣẹ tó kọ fún yín,+ ni kí ẹ máa pa mọ́ délẹ̀délẹ̀, ẹ ò sì gbọ́dọ̀ sin àwọn ọlọ́run míì. 38 Ẹ ò gbọ́dọ̀ gbàgbé májẹ̀mú tí mo bá yín dá,+ ẹ ò sì gbọ́dọ̀ sin àwọn ọlọ́run míì. 39 Àmọ́ Jèhófà Ọlọ́run yín ni kí ẹ máa sìn, nítorí òun ni ẹni tó máa gbà yín lọ́wọ́ gbogbo àwọn ọ̀tá yín.”
40 Àmọ́ wọn ò ṣègbọràn, wọ́n sì ń ṣe ẹ̀sìn* wọn àtẹ̀yìnwá.+ 41 Torí náà, àwọn orílẹ̀-èdè yìí ń bẹ̀rù Jèhófà,+ àmọ́ wọ́n tún ń sin àwọn ère gbígbẹ́ wọn. Àwọn ọmọ wọn àti àwọn ọmọ ọmọ wọn ń ṣe bí àwọn baba ńlá wọn ti ṣe, títí di òní yìí.
18 Ní ọdún kẹta Hóṣéà+ ọmọ Élà ọba Ísírẹ́lì, Hẹsikáyà+ ọmọ Áhásì+ ọba Júdà di ọba. 2 Ẹni ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n (25) ni nígbà tó jọba, ọdún mọ́kàndínlọ́gbọ̀n (29) ló sì fi ṣàkóso ní Jerúsálẹ́mù. Orúkọ ìyá rẹ̀ ni Ábì* ọmọ Sekaráyà.+ 3 Ó ń ṣe ohun tí ó tọ́ ní ojú Jèhófà+ bí Dáfídì baba ńlá rẹ̀ ti ṣe.+ 4 Òun ló mú àwọn ibi gíga kúrò,+ tó fọ́ àwọn ọwọ̀n òrìṣà sí wẹ́wẹ́, tó sì gé òpó òrìṣà*+ lulẹ̀. Ó tún fọ́ ejò bàbà tí Mósè ṣe;+ torí pé títí di àkókò yẹn ni àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ń mú ẹbọ rú èéfín sí i, tí wọ́n sì ń pè é ní òrìṣà ejò bàbà.* 5 Ó gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà+ Ọlọ́run Ísírẹ́lì; kò sí ẹnì kankan tó dà bíi rẹ̀ nínú gbogbo àwọn ọba Júdà tó wà ṣáájú rẹ̀ àti àwọn tí wọ́n jẹ lẹ́yìn rẹ̀. 6 Kò fi Jèhófà sílẹ̀.+ Kò yà kúrò lẹ́yìn rẹ̀; ó ń pa àwọn àṣẹ tí Jèhófà fún Mósè mọ́. 7 Jèhófà sì wà pẹ̀lú rẹ̀. Ó ń hùwà ọgbọ́n níbikíbi tó bá lọ. Ó ṣọ̀tẹ̀ sí ọba Ásíríà, ó sì kọ̀ láti sìn ín.+ 8 Ó tún ṣẹ́gun àwọn Filísínì+ títí dé Gásà àti àwọn ìpínlẹ̀ rẹ̀, láti ilé ìṣọ́ títí dé ìlú olódi.*
9 Ní ọdún kẹrin Ọba Hẹsikáyà, ìyẹn ní ọdún keje Hóṣéà+ ọmọ Élà ọba Ísírẹ́lì, Ṣálímánésà ọba Ásíríà wá gbéjà ko Samáríà, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í dó tì í.+ 10 Wọ́n gbà á+ ní òpin ọdún mẹ́ta; ní ọdún kẹfà Hẹsikáyà, ìyẹn ní ọdún kẹsàn-án Hóṣéà ọba Ísírẹ́lì, wọ́n gba Samáríà. 11 Lẹ́yìn ìyẹn, ọba Ásíríà kó Ísírẹ́lì lọ sí ìgbèkùn+ ní Ásíríà, ó sì ní kí wọ́n máa gbé ní Hálà àti ní Hábórì níbi odò Gósánì àti ní àwọn ìlú àwọn ará Mídíà.+ 12 Ohun tó fa èyí ni pé wọn kò fetí sí ohùn Jèhófà Ọlọ́run wọn, wọ́n ń da májẹ̀mú rẹ̀, ìyẹn gbogbo ohun tí Mósè ìránṣẹ́ Jèhófà pa láṣẹ.+ Wọn ò fetí sílẹ̀, wọn ò sì ṣègbọràn.
13 Ní ọdún kẹrìnlá Ọba Hẹsikáyà, Senakérúbù ọba Ásíríà+ wá gbéjà ko gbogbo ìlú olódi Júdà, ó sì gbà wọ́n.+ 14 Nítorí náà, Hẹsikáyà ọba Júdà ránṣẹ́ sí ọba Ásíríà ní Lákíṣì pé: “Èmi ni mo jẹ̀bi. Má ṣe bá mi jà mọ́, ohunkóhun tí o bá ní kí n san ni màá san.” Ni ọba Ásíríà bá bu ọgọ́rùn-ún mẹ́ta (300) tálẹ́ńtì* fàdákà àti ọgbọ̀n (30) tálẹ́ńtì wúrà lé Hẹsikáyà ọba Júdà. 15 Torí náà, Hẹsikáyà fi gbogbo fàdákà tí wọ́n rí ní ilé Jèhófà àti ní àwọn ibi ìṣúra ilé* ọba+ lélẹ̀. 16 Lákòókò yẹn, Hẹsikáyà yọ* àwọn ilẹ̀kùn tẹ́ńpìlì+ Jèhófà kúrò àti àwọn òpó ilẹ̀kùn tí Hẹsikáyà ọba Júdà fúnra rẹ̀ fi wúrà bò,+ ó sì kó wọn fún ọba Ásíríà.
17 Ọba Ásíríà wá rán àwọn mẹ́ta tí orúkọ oyè wọn ń jẹ́ Tátánì* àti Rábúsárísì* àti Rábúṣákè* pẹ̀lú ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọmọ ogun láti Lákíṣì+ sí Ọba Hẹsikáyà ní Jerúsálẹ́mù.+ Wọ́n lọ sí Jerúsálẹ́mù, wọ́n sì dúró síbi tí adágún omi tó wà lápá òkè ń gbà, èyí tó wà lójú ọ̀nà tó lọ sí pápá alágbàfọ̀.+ 18 Nígbà tí wọ́n pe ọba pé kó jáde, Élíákímù+ ọmọ Hilikáyà, ẹni tó ń bójú tó agbo ilé* àti Ṣẹ́bínà+ akọ̀wé pẹ̀lú Jóà ọmọ Ásáfù akọ̀wé ìrántí jáde wá bá wọn.
19 Torí náà, Rábúṣákè sọ fún wọn pé: “Ẹ jọ̀ọ́, ẹ sọ fún Hẹsikáyà pé, ‘Ohun tí ọba ńlá, ọba Ásíríà sọ nìyí: “Kí lo gbọ́kàn lé?+ 20 Ò ń sọ pé, ‘Mo ní ọgbọ́n àti agbára láti jagun,’ àmọ́ ọ̀rọ̀ ẹnu lásán nìyẹn. Ta lo gbẹ́kẹ̀ lé, tí o fi gbójúgbóyà ṣọ̀tẹ̀ sí mi?+ 21 Wò ó! Ṣé Íjíbítì+ tó dà bí esùsú* fífọ́ yìí lo gbẹ́kẹ̀ lé, tó jẹ́ pé bí èèyàn bá fara tì í, ṣe ló máa wọ àtẹ́lẹwọ́ rẹ̀, tí á sì gún un yọ? Bí Fáráò ọba Íjíbítì ṣe rí nìyẹn sí gbogbo àwọn tó gbẹ́kẹ̀ lé e. 22 Tí ẹ bá sì sọ fún mi pé, ‘Jèhófà Ọlọ́run wa ni a gbẹ́kẹ̀ lé,’+ ṣé òun kọ́ ni Hẹsikáyà mú àwọn ibi gíga rẹ̀ àti àwọn pẹpẹ rẹ̀ kúrò,+ tó sì sọ fún Júdà àti Jerúsálẹ́mù pé, ‘Iwájú pẹpẹ tó wà ní Jerúsálẹ́mù yìí ni kí ẹ ti máa forí balẹ̀’?”’+ 23 Ní báyìí, ẹ wò ó, olúwa mi ọba Ásíríà pè yín níjà: Ẹ jẹ́ kí n fún yín ní ẹgbẹ̀rún méjì (2,000) ẹṣin, ká wá wò ó bóyá ẹ máa lè rí àwọn agẹṣin tó máa gùn wọ́n.+ 24 Báwo wá ni ẹ ṣe lè borí gómìnà kan ṣoṣo tó kéré jù lára àwọn ìránṣẹ́ olúwa mi, nígbà tó jẹ́ pé Íjíbítì lẹ gbẹ́kẹ̀ lé pé ó máa fún yín ní àwọn kẹ̀kẹ́ ẹṣin àti àwọn agẹṣin? 25 Ṣé láìgba àṣẹ lọ́wọ́ Jèhófà ni mo wá gbéjà ko ibí yìí láti pa á run ni? Jèhófà fúnra rẹ̀ sọ fún mi pé, ‘Lọ gbéjà ko ilẹ̀ yìí, kí o sì pa á run.’”
26 Ni Élíákímù ọmọ Hilikáyà àti Ṣẹ́bínà+ pẹ̀lú Jóà bá sọ fún Rábúṣákè+ pé: “Jọ̀ọ́, bá àwa ìránṣẹ́ rẹ sọ̀rọ̀ ní èdè Árámáíkì*+ torí a gbọ́ èdè náà; má fi èdè àwọn Júù bá wa sọ̀rọ̀ lójú àwọn èèyàn tó wà lórí ògiri.”+ 27 Ṣùgbọ́n Rábúṣákè sọ fún wọn pé: “Ṣé ẹ̀yin àti olúwa yín nìkan ni olúwa mi ní kí n sọ ọ̀rọ̀ yìí fún ni? Ṣé kò tún rán mi sí àwọn ọkùnrin tó ń jókòó lórí ògiri, àwọn tó máa jẹ ìgbẹ́ ara wọn, tí wọ́n sì máa mu ìtọ̀ ara wọn pẹ̀lú yín?”
28 Rábúṣákè bá dìde, ó gbé ohùn rẹ̀ sókè, ó sì fi èdè àwọn Júù sọ̀rọ̀, ó ní: “Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ ọba ńlá, ọba Ásíríà.+ 29 Ohun tí ọba sọ nìyí, ‘Ẹ má ṣe jẹ́ kí Hẹsikáyà tàn yín jẹ, nítorí kò lè gbà yín kúrò lọ́wọ́ mi.+ 30 Ẹ má sì jẹ́ kí Hẹsikáyà mú kí ẹ gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, bó ṣe ń sọ pé: “Ó dájú pé Jèhófà máa gbà wá, a ò sì ní fi ìlú yìí lé ọba Ásíríà lọ́wọ́.”+ 31 Ẹ má fetí sí Hẹsikáyà, torí ohun tí ọba Ásíríà sọ nìyí: “Ẹ bá mi ṣe àdéhùn àlàáfíà, kí ẹ sì túúbá,* kálukú yín á máa jẹ látinú àjàrà rẹ̀ àti igi ọ̀pọ̀tọ́ rẹ̀, á sì máa mu omi látinú kòtò omi rẹ̀, 32 títí màá fi wá kó yín lọ sí ilẹ̀ tó dà bí ilẹ̀ yín,+ ilẹ̀ ọkà àti ti wáìnì tuntun, ilẹ̀ oúnjẹ àti ti àwọn ọgbà àjàrà, ilẹ̀ àwọn igi ólífì àti ti oyin. Kí ẹ lè máa wà láàyè nìṣó, kí ẹ má sì kú. Ẹ má fetí sí Hẹsikáyà, nítorí ṣe ló ń ṣì yín lọ́nà bó ṣe ń sọ pé, ‘Jèhófà máa gbà wá.’ 33 Ǹjẹ́ ìkankan lára ọlọ́run àwọn orílẹ̀-èdè ti gba ilẹ̀ wọn kúrò lọ́wọ́ ọba Ásíríà? 34 Ibo ni àwọn ọlọ́run Hámátì+ àti ti Áápádì wà? Ibo ni àwọn ọlọ́run Séfáfáímù,+ Hénà àti ti Ífà wà? Ǹjẹ́ wọ́n gba Samáríà kúrò lọ́wọ́ mi?+ 35 Èwo nínú gbogbo ọlọ́run àwọn ilẹ̀ náà ló ti gba ilẹ̀ wọn kúrò lọ́wọ́ mi, tí Jèhófà yóò fi gba Jerúsálẹ́mù kúrò lọ́wọ́ mi?”’”+
36 Àmọ́ àwọn èèyàn náà dákẹ́, wọn ò fún un lésì kankan, nítorí àṣẹ ọba ni pé, “Ẹ ò gbọ́dọ̀ dá a lóhùn.”+ 37 Ṣùgbọ́n Élíákímù ọmọ Hilikáyà, ẹni tó ń bójú tó agbo ilé* àti Ṣẹ́bínà akọ̀wé pẹ̀lú Jóà ọmọ Ásáfù akọ̀wé ìrántí wá sọ́dọ̀ Hẹsikáyà, pẹ̀lú ẹ̀wù yíya lọ́rùn wọn, wọ́n sì sọ àwọn ọ̀rọ̀ Rábúṣákè fún un.
19 Gbàrà tí Ọba Hẹsikáyà gbọ́ ọ̀rọ̀ náà, ó fa ẹ̀wù rẹ̀ ya, ó fi aṣọ ọ̀fọ̀* bora, ó sì lọ sínú ilé Jèhófà.+ 2 Lẹ́yìn náà, ó rán Élíákímù, ẹni tó ń bójú tó agbo ilé* àti Ṣẹ́bínà akọ̀wé pẹ̀lú àwọn àgbààgbà nínú àwọn àlùfáà, wọ́n fi aṣọ ọ̀fọ̀* bora, ó sì rán wọn sí wòlíì Àìsáyà,+ ọmọ Émọ́ọ̀sì. 3 Wọ́n sọ fún un pé: “Ohun tí Hẹsikáyà sọ nìyí, ‘Ọjọ́ òní jẹ́ ọjọ́ wàhálà àti ti ìbáwí* àti ti ìtìjú; nítorí a dà bí aboyún tó fẹ́ bímọ,* àmọ́ tí kò ní okun láti bí i.+ 4 Bóyá Jèhófà Ọlọ́run rẹ máa gbọ́ gbogbo ọ̀rọ̀ Rábúṣákè tí olúwa rẹ̀ ọba Ásíríà rán láti pẹ̀gàn Ọlọ́run alààyè,+ tí á sì pè é wá jíhìn nítorí àwọn ọ̀rọ̀ tí Jèhófà Ọlọ́run rẹ ti gbọ́. Torí náà, gbàdúrà nítorí àṣẹ́kù+ tó yè bọ́ yìí.’”
5 Nítorí náà, àwọn ìránṣẹ́ Ọba Hẹsikáyà lọ sọ́dọ̀ Àìsáyà,+ 6 Àìsáyà sì sọ fún wọn pé: “Ẹ sọ fún olúwa yín pé, ‘Ohun tí Jèhófà sọ nìyí: “Má bẹ̀rù+ nítorí àwọn ọ̀rọ̀ tí o gbọ́, àwọn ọ̀rọ̀ tí àwọn ẹmẹ̀wà* ọba Ásíríà fi pẹ̀gàn mi.+ 7 Wò ó, màá fi ohun kan sí i lọ́kàn,* ó máa gbọ́ ìròyìn kan, á sì pa dà sí ilẹ̀ rẹ̀; màá sì jẹ́ kí wọ́n fi idà pa á ní ilẹ̀ òun fúnra rẹ̀.”’”+
8 Lẹ́yìn tí Rábúṣákè gbọ́ pé ọba Ásíríà ti kúrò ní Lákíṣì,+ ó pa dà sọ́dọ̀ rẹ̀, ó sì rí i tó ń bá Líbínà jà.+ 9 Ọba wá gbọ́ tí wọ́n sọ nípa Tíhákà ọba Etiópíà pé: “Wò ó, ó ti jáde láti wá bá ọ jà.” Nítorí náà, ó tún rán àwọn òjíṣẹ́+ sí Hẹsikáyà pé: 10 “Ẹ sọ fún Hẹsikáyà ọba Júdà pé, ‘Má ṣe jẹ́ kí Ọlọ́run rẹ tí o gbẹ́kẹ̀ lé tàn ọ́ jẹ pé: “A kò ní fi Jerúsálẹ́mù lé ọba Ásíríà lọ́wọ́.”+ 11 Wò ó! O ti gbọ́ ohun tí àwọn ọba Ásíríà ṣe sí gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè, bí wọ́n ṣe pa wọ́n run.+ Ṣé o rò pé o lè bọ́ lọ́wọ́ wa ni? 12 Ǹjẹ́ àwọn ọlọ́run àwọn orílẹ̀-èdè tí àwọn baba ńlá mi pa run gbà wọ́n? Ibo ni Gósánì, Háránì,+ Réséfù àti àwọn èèyàn Édẹ́nì tó wà ní Tẹli-ásárì wà? 13 Ibo ni ọba Hámátì, ọba Áápádì, ọba àwọn ìlú Séfáfáímù, ọba Hénà àti ọba Ífà+ wà?’”
14 Hẹsikáyà gba àwọn lẹ́tà náà lọ́wọ́ àwọn òjíṣẹ́ náà, ó sì kà wọ́n. Lẹ́yìn náà, Hẹsikáyà lọ sí ilé Jèhófà, ó sì tẹ́ wọn* síwájú Jèhófà.+ 15 Hẹsikáyà wá bẹ̀rẹ̀ sí í gbàdúrà+ níwájú Jèhófà, ó sọ pé: “Ìwọ Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì, tí o jókòó sórí ìtẹ́ lókè* àwọn kérúbù,+ ìwọ nìkan ni Ọlọ́run tòótọ́ lórí gbogbo ìjọba ayé.+ Ìwọ lo dá ọ̀run àti ayé. 16 Fetí sílẹ̀, Jèhófà, kí o sì gbọ́!+ La ojú rẹ,+ Jèhófà, kí o sì rí i! Kí o gbọ́ àwọn ọ̀rọ̀ tí Senakérúbù fi ránṣẹ́ láti pẹ̀gàn Ọlọ́run alààyè. 17 Jèhófà, òótọ́ ni pé àwọn ọba Ásíríà ti pa àwọn orílẹ̀-èdè àti ilẹ̀ wọn run.+ 18 Wọ́n sì ti ju àwọn ọlọ́run wọn sínú iná, nítorí wọn kì í ṣe ọlọ́run,+ iṣẹ́ ọwọ́ èèyàn ni wọ́n,+ wọ́n jẹ́ igi àti òkúta. Ìdí nìyẹn tí wọ́n fi lè pa wọ́n run. 19 Àmọ́ ní báyìí, ìwọ Jèhófà Ọlọ́run wa, jọ̀ọ́ gbà wá lọ́wọ́ rẹ̀, kí gbogbo ìjọba ayé lè mọ̀ pé ìwọ Jèhófà nìkan ṣoṣo ni Ọlọ́run.”+
20 Àìsáyà ọmọ Émọ́ọ̀sì wá ránṣẹ́ sí Hẹsikáyà pé: “Ohun tí Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì sọ nìyí, ‘Mo ti gbọ́ àdúrà tí o gbà+ sí mi nítorí Senakérúbù ọba Ásíríà.+ 21 Ọ̀rọ̀ tí Jèhófà sọ nípa rẹ̀ nìyí:
“Wúńdíá ọmọbìnrin Síónì pẹ̀gàn rẹ, ó ti fi ọ́ ṣẹ̀sín.
Ọmọbìnrin Jerúsálẹ́mù mi orí rẹ̀ sí ọ.
22 Ta lo pẹ̀gàn, tí o sì sọ̀rọ̀ òdì sí?+
Ta lo gbé ohùn rẹ sókè sí,+
Tí o sì gbé ojú rẹ ga sí?
Ẹni Mímọ́ Ísírẹ́lì mà ni!+
23 O tipasẹ̀ àwọn òjíṣẹ́ rẹ+ pẹ̀gàn Jèhófà,+ o sọ pé,
‘Pẹ̀lú ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn kẹ̀kẹ́ ogun mi,
Màá gun ibi gíga àwọn òkè,
Ibi tó jìnnà jù lọ ní Lẹ́bánónì.
Ṣe ni màá gé àwọn igi kédárì rẹ̀ tó ga fíofío lulẹ̀, àwọn ààyò igi júnípà rẹ̀.
Màá wọ ìpẹ̀kun ibi tó máa ń sá sí, igbó kìjikìji rẹ̀.
24 Màá gbẹ́ kànga, màá sì mu àjèjì omi;
Màá fi àtẹ́lẹsẹ̀ mi mú kí gbogbo odò* Íjíbítì gbẹ.’
25 Ṣé o ò tíì gbọ́ ni? Tipẹ́tipẹ́ ni mo ti pinnu rẹ̀.*+
Láti ọ̀pọ̀ ọjọ́ sẹ́yìn ni mo ti ṣètò* rẹ̀.+
Ní báyìí, màá ṣe é.+
Wàá sọ àwọn ìlú olódi di àwókù.+
26 Àwọn tó ń gbé inú wọn á di aláìlágbára;
Jìnnìjìnnì á bá wọn, ojú á sì tì wọ́n.
Wọ́n á rọ bí ewéko pápá àti bí koríko tútù ṣe máa ń rọ,+
Bíi koríko orí òrùlé tí atẹ́gùn ìlà oòrùn ti jó gbẹ.
27 Àmọ́, mo mọ ìgbà tí o bá jókòó, ìgbà tí o bá jáde àti ìgbà tí o bá wọlé,+
Àti ìgbà tí inú rẹ bá ru sí mi,+
28 Torí bí inú rẹ ṣe ń ru sí mi+ àti bí o ṣe ń ké ramúramù ti dé etí mi.+
Torí náà, màá fi ìwọ̀ mi kọ́ imú rẹ,+ màá fi ìjánu mi sáàárín ètè rẹ,
Ọ̀nà tí o gbà wá ni màá sì mú ọ gbà pa dà.”+
29 “‘Ohun tó máa jẹ́ àmì fún ọ* nìyí: Lọ́dún yìí, ẹ ó jẹ ohun tó lalẹ̀ hù;* ní ọdún kejì, ọkà tó hù látinú ìyẹn ni ẹ ó jẹ;+ àmọ́ ní ọdún kẹta, ẹ ó fúnrúgbìn, ẹ ó sì kórè, ẹ ó gbin àwọn ọgbà àjàrà, ẹ ó sì jẹ èso wọn.+ 30 Ìyókù àwọn ará ilé Júdà tó sá àsálà máa ta gbòǹgbò nísàlẹ̀,+ wọ́n á sì so èso lókè. 31 Nítorí àṣẹ́kù kan máa jáde wá láti Jerúsálẹ́mù, àwọn tó là á já sì máa jáde wá láti Òkè Síónì. Ìtara Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun máa ṣe èyí.+
32 “‘Torí náà, ohun tí Jèhófà sọ nípa ọba Ásíríà nìyí:+
“Kò ní wọ inú ìlú yìí+
Bẹ́ẹ̀ ni kò ní ta ọfà sí ibẹ̀
Tàbí kó fi apata dojú kọ ọ́
Bẹ́ẹ̀ sì ni kò ní mọ òkìtì láti dó tì í.+
33 Ọ̀nà tó gbà wá ló máa gbà pa dà;
Kò ní wọ inú ìlú yìí,” ni Jèhófà wí.
35 Ní òru ọjọ́ yẹn, áńgẹ́lì Jèhófà jáde lọ, ó sì pa ọ̀kẹ́ mẹ́sàn-án ó lé ẹgbẹ̀rún márùn-ún (185,000) ọkùnrin nínú ibùdó àwọn ará Ásíríà.+ Nígbà tí àwọn èèyàn jí láàárọ̀ kùtù, wọ́n rí òkú nílẹ̀ bẹẹrẹbẹ.+ 36 Torí náà, Senakérúbù ọba Ásíríà kúrò níbẹ̀, ó pa dà sí Nínéfè,+ ó sì ń gbé ibẹ̀.+ 37 Bó ṣe ń forí balẹ̀ ní ilé* Nísírọ́kì ọlọ́run rẹ̀, àwọn ọmọ rẹ̀, Adiramélékì àti Ṣárésà fi idà pa á,+ wọ́n sì sá lọ sí ilẹ̀ Árárátì.+ Esari-hádónì+ ọmọ rẹ̀ sì jọba ní ipò rẹ̀.
20 Ní àkókò náà, Hẹsikáyà ṣàìsàn dé ojú ikú.+ Wòlíì Àìsáyà ọmọ Émọ́ọ̀sì wá bá a, ó sì sọ fún un pé, “Ohun tí Jèhófà sọ nìyí: ‘Sọ ohun tí agbo ilé rẹ máa ṣe fún wọn, torí pé o máa kú; o ò ní yè é.’”+ 2 Ni ó bá yíjú sí ògiri, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í gbàdúrà sí Jèhófà, ó ní: 3 “Mo bẹ̀ ọ́, Jèhófà, jọ̀ọ́ rántí bí mo ṣe fi òtítọ́ àti gbogbo ọkàn mi rìn níwájú rẹ, ohun tó dáa ní ojú rẹ sì ni mo ṣe.”+ Hẹsikáyà sì bẹ̀rẹ̀ sí í sunkún pẹ̀rẹ̀pẹ̀rẹ̀.
4 Àìsáyà kò tíì dé àgbàlá àárín nígbà tí Jèhófà bá a sọ̀rọ̀ pé:+ 5 “Pa dà lọ sọ fún Hẹsikáyà aṣáájú àwọn èèyàn mi pé, ‘Ohun tí Jèhófà Ọlọ́run Dáfídì baba ńlá rẹ sọ nìyí: “Mo ti gbọ́ àdúrà rẹ. Mo ti rí omijé rẹ.+ Wò ó, màá mú ọ lára dá.+ Ní ọ̀túnla, wàá lọ sí ilé Jèhófà.+ 6 Màá fi ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún (15) kún ọjọ́ ayé* rẹ, màá gba ìwọ àti ìlú yìí lọ́wọ́ ọba Ásíríà,+ màá sì gbèjà ìlú yìí nítorí orúkọ mi àti nítorí Dáfídì ìránṣẹ́ mi.”’”+
7 Àìsáyà wá sọ pé: “Ẹ mú ìṣù ọ̀pọ̀tọ́ gbígbẹ wá.” Nítorí náà, wọ́n mú un wá, wọ́n sì fi í sí eéwo náà, ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, ara rẹ̀ yá.+
8 Hẹsikáyà ti béèrè lọ́wọ́ Àìsáyà pé: “Àmì+ wo ló máa jẹ́ kó dá mi lójú pé Jèhófà máa mú mi lára dá àti pé màá lè lọ sí ilé Jèhófà ní ọjọ́ kẹta?” 9 Àìsáyà fèsì pé: “Àmì tí Jèhófà fún ọ nìyí láti mú un dá ọ lọ́jú pé Jèhófà máa mú ọ̀rọ̀ tó sọ ṣẹ: Ṣé o fẹ́ kí òjìji tó wà lórí àtẹ̀gùn* lọ síwájú ní ìgbésẹ̀ mẹ́wàá tàbí kó pa dà sẹ́yìn ní ìgbésẹ̀ mẹ́wàá?”+ 10 Hẹsikáyà sọ pé: “Ó rọrùn fún òjìji láti lọ síwájú ní ìgbésẹ̀ mẹ́wàá, àmọ́ kì í ṣe bíi pé kò pa dà sẹ́yìn ní ìgbésẹ̀ mẹ́wàá.” 11 Torí náà, wòlíì Àìsáyà ké pe Jèhófà, Ó sì mú kí òjìji tó wà lórí àtẹ̀gùn Áhásì pa dà sẹ́yìn ní ìgbésẹ̀ mẹ́wàá lẹ́yìn tó ti kọ́kọ́ lọ síwájú lórí àtẹ̀gùn náà.+
12 Ní àkókò yẹn, ọba Bábílónì, ìyẹn Berodaki-báládánì ọmọ Báládánì fi àwọn lẹ́tà àti ẹ̀bùn ránṣẹ́ sí Hẹsikáyà, torí ó gbọ́ pé Hẹsikáyà ṣàìsàn.+ 13 Hẹsikáyà kí wọn káàbọ̀,* ó sì fi gbogbo ohun tó wà nínú ilé ìṣúra+ rẹ̀ hàn wọ́n, ìyẹn fàdákà, wúrà, òróró básámù àti àwọn òróró míì tó ṣeyebíye pẹ̀lú ilé tó ń kó ohun ìjà sí àti gbogbo ohun tó wà nínú àwọn ibi ìṣúra rẹ̀. Kò sí nǹkan tí Hẹsikáyà kò fi hàn wọ́n nínú ilé* rẹ̀ àti nínú gbogbo agbègbè tó wà lábẹ́ àkóso rẹ̀.
14 Lẹ́yìn náà, wòlíì Àìsáyà wá sọ́dọ̀ Ọba Hẹsikáyà, ó sì béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé: “Kí ni àwọn ọkùnrin yìí sọ, ibo ni wọ́n sì ti wá?” Torí náà, Hẹsikáyà sọ pé: “Ilẹ̀ tó jìnnà ni wọ́n ti wá, láti Bábílónì.”+ 15 Ó tún béèrè pé: “Kí ni wọ́n rí nínú ilé* rẹ?” Hẹsikáyà fèsì pé: “Gbogbo ohun tó wà nínú ilé* mi ni wọ́n rí. Kò sí nǹkan kan tó wà nínú àwọn ibi ìṣúra mi tí mi ò fi hàn wọ́n.”
16 Àìsáyà wá sọ fún Hẹsikáyà pé: “Gbọ́ ọ̀rọ̀ Jèhófà,+ 17 ‘Wò ó! Ọjọ́ ń bọ̀ tí wọ́n máa kó gbogbo ohun tó wà nínú ilé* rẹ àti gbogbo ohun tí àwọn baba ńlá rẹ ti kó jọ títí di òní yìí lọ sí Bábílónì.+ Kò ní ku nǹkan kan,’ ni Jèhófà wí. 18 ‘Wọ́n á mú àwọn kan lára àwọn ọmọ tí o máa bí,+ wọ́n á sì di òṣìṣẹ́ ààfin ní ààfin ọba Bábílónì.’”+
19 Ni Hẹsikáyà bá sọ fún Àìsáyà pé: “Ọ̀rọ̀ Jèhófà tí o sọ dára.”+ Ó wá fi kún un pé: “Tí àlàáfíà àti ìfọkànbalẹ̀* bá ti wà lásìkò* mi,+ ó ti dáa.”
20 Ní ti ìyókù ìtàn Hẹsikáyà àti gbogbo agbára rẹ̀ àti bí ó ṣe ṣe adágún odò+ àti ọ̀nà omi àti bí ó ṣe gbé omi wá sínú ìlú,+ ǹjẹ́ kò wà lákọsílẹ̀ nínú ìwé ìtàn ìgbà àwọn ọba Júdà? 21 Níkẹyìn, Hẹsikáyà sinmi pẹ̀lú àwọn baba ńlá rẹ̀;+ Mánásè+ ọmọ rẹ̀ sì jọba ní ipò rẹ̀.+
21 Ọmọ ọdún méjìlá (12) ni Mánásè+ nígbà tó jọba, ọdún márùndínlọ́gọ́ta (55) ló sì fi ṣàkóso ní Jerúsálẹ́mù.+ Orúkọ ìyá rẹ̀ ni Héfísíbà. 2 Ó ṣe ohun tó burú ní ojú Jèhófà, torí pé ó ń ṣe àwọn ohun ìríra bíi ti àwọn orílẹ̀-èdè+ tí Jèhófà lé kúrò níwájú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.+ 3 Ó tún àwọn ibi gíga kọ́, èyí tí Hẹsikáyà bàbá rẹ̀ pa run,+ ó mọ àwọn pẹpẹ fún Báálì, ó sì ṣe òpó òrìṣà,*+ bí Áhábù ọba Ísírẹ́lì ti ṣe.+ Ó forí balẹ̀ fún gbogbo ọmọ ogun ọ̀run, ó sì ń sìn wọ́n.+ 4 Ó tún mọ àwọn pẹpẹ sí ilé Jèhófà,+ níbi tí Jèhófà sọ nípa rẹ̀ pé: “Inú Jerúsálẹ́mù ni màá fi orúkọ mi sí.”+ 5 Ó mọ àwọn pẹpẹ fún gbogbo ọmọ ogun ọ̀run+ sí àgbàlá méjì nínú ilé Jèhófà.+ 6 Ó sun ọmọ rẹ̀ nínú iná; ó ń pidán, ó ń woṣẹ́,+ ó sì yan àwọn abẹ́mìílò àti àwọn woṣẹ́woṣẹ́.+ Ohun búburú tó pọ̀ gan-an ló ṣe lójú Jèhófà, ó sì tipa bẹ́ẹ̀ mú un bínú.
7 Ó gbé ère òpó òrìṣà*+ tó gbẹ́ wá sínú ilé tí Jèhófà sọ nípa rẹ̀ fún Dáfídì àti Sólómọ́nì ọmọ rẹ̀ pé: “Inú ilé yìí àti ní Jerúsálẹ́mù, tí mo ti yàn nínú gbogbo ẹ̀yà Ísírẹ́lì, ni màá fi orúkọ mi sí títí láé.+ 8 Mi ò tún ní mú kí Ísírẹ́lì rìn gbéregbère kúrò ní ilẹ̀ tí mo fún àwọn baba ńlá wọn,+ tí wọ́n bá ṣáà ti rí i pé wọ́n tẹ̀ lé gbogbo ohun tí mo pa láṣẹ fún wọn,+ ìyẹn gbogbo Òfin tí Mósè ìránṣẹ́ mi pa láṣẹ fún wọn pé kí wọ́n máa tẹ̀ lé.” 9 Àmọ́, wọn kò ṣègbọràn, Mánásè sì ń ṣì wọ́n lọ́nà, ó ń mú kí wọ́n ṣe ohun tó burú ju ti àwọn orílẹ̀-èdè tí Jèhófà pa run kúrò níwájú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.+
10 Jèhófà ń gbẹnu àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ wòlíì sọ̀rọ̀ léraléra+ pé: 11 “Mánásè ọba Júdà ṣe gbogbo àwọn ohun ìríra yìí; ó ṣe ohun tó burú ju ti gbogbo àwọn Ámórì+ tó wà ṣáájú rẹ̀,+ ó sì fi àwọn òrìṣà ẹ̀gbin* rẹ̀ mú Júdà dẹ́ṣẹ̀. 12 Nítorí náà, ohun tí Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì sọ nìyí: ‘Wò ó, màá fa àjálù bá Jerúsálẹ́mù+ àti Júdà, tó jẹ́ pé bí ẹnikẹ́ni bá gbọ́ nípa rẹ̀, etí rẹ̀ méjèèjì á hó yee.+ 13 Màá na okùn ìdíwọ̀n+ tí a lò fún Samáríà+ sórí Jerúsálẹ́mù àti irinṣẹ́ tí a fi ń mú nǹkan tẹ́jú* tí a lò fún ilé Áhábù,+ màá sì fọ Jerúsálẹ́mù mọ́ bí ẹni fọ abọ́ mọ́, màá nù ún, màá sì dojú rẹ̀ dé.+ 14 Màá pa àwọn tó ṣẹ́ kù nínú ogún mi tì,+ màá sì fi wọ́n lé àwọn ọ̀tá wọn lọ́wọ́, àwọn ọ̀tá wọn á kó wọn lẹ́rú, wọ́n á sì kó wọn lẹ́rù,+ 15 nítorí pé wọ́n ṣe ohun tó burú ní ojú mi, tí wọ́n sì ń mú mi bínú láti ọjọ́ tí àwọn baba ńlá wọn ti jáde kúrò ní Íjíbítì títí di òní yìí.’”+
16 Mánásè ta ẹ̀jẹ̀ àwọn aláìṣẹ̀ sílẹ̀ lọ́pọ̀lọpọ̀ débi pé ó kún Jerúsálẹ́mù láti ìkángun kan dé ìkángun kejì,+ yàtọ̀ sí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ èyí tí ó mú Júdà ṣẹ̀, tí wọ́n fi ń ṣe ohun tó burú ní ojú Jèhófà. 17 Ní ti ìyókù ìtàn Mánásè àti gbogbo ohun tí ó ṣe àti ẹ̀ṣẹ̀ tí ó dá, ǹjẹ́ wọn ò wà lákọsílẹ̀ nínú ìwé ìtàn ìgbà àwọn ọba Júdà? 18 Níkẹyìn, Mánásè sinmi pẹ̀lú àwọn baba ńlá rẹ̀, wọ́n sì sin ín sínú ọgbà ilé rẹ̀, nínú ọgbà Úúsà;+ Ámọ́nì ọmọ rẹ̀ sì jọba ní ipò rẹ̀.
19 Ẹni ọdún méjìlélógún (22) ni Ámọ́nì+ nígbà tó jọba, ọdún méjì ló sì fi ṣàkóso ní Jerúsálẹ́mù.+ Orúkọ ìyá rẹ̀ ni Méṣúlémétì ọmọ Hárúsì láti Jótíbà. 20 Ó ń ṣe ohun tó burú ní ojú Jèhófà bí Mánásè bàbá rẹ̀ ti ṣe.+ 21 Ó ń rìn ní gbogbo ọ̀nà tí bàbá rẹ̀ rìn, ó ń sin àwọn òrìṣà ẹ̀gbin tí bàbá rẹ̀ sìn, ó sì ń forí balẹ̀ fún wọn.+ 22 Torí náà, ó fi Jèhófà Ọlọ́run àwọn baba ńlá rẹ̀ sílẹ̀, kò sì rìn ní ọ̀nà Jèhófà.+ 23 Níkẹyìn, àwọn ìránṣẹ́ Ámọ́nì dìtẹ̀ mọ́ ọn, wọ́n sì pa á nínú ilé rẹ̀. 24 Àmọ́ àwọn èèyàn ilẹ̀ náà pa gbogbo àwọn tó dìtẹ̀ mọ́ Ọba Ámọ́nì, wọ́n sì fi Jòsáyà ọmọ rẹ̀ jọba ní ipò rẹ̀.+ 25 Ní ti ìyókù ìtàn Ámọ́nì àti ohun tí ó ṣe, ǹjẹ́ kò wà lákọsílẹ̀ nínú ìwé ìtàn ìgbà àwọn ọba Júdà? 26 Nítorí náà, wọ́n sin ín sí sàréè rẹ̀ nínú ọgbà Úúsà,+ Jòsáyà+ ọmọ rẹ̀ sì jọba ní ipò rẹ̀.
22 Ọmọ ọdún mẹ́jọ ni Jòsáyà+ nígbà tó jọba, ọdún mọ́kànlélọ́gbọ̀n (31) ló sì fi ṣàkóso ní Jerúsálẹ́mù.+ Orúkọ ìyá rẹ̀ ni Jédídà ọmọ Ádáyà láti Bósíkátì.+ 2 Ó ṣe ohun tí ó tọ́ ní ojú Jèhófà, ó rìn ní gbogbo ọ̀nà Dáfídì baba ńlá rẹ̀,+ kò sì yà sí ọ̀tún tàbí sí òsì.
3 Ní ọdún kejìdínlógún Ọba Jòsáyà, ọba rán Ṣáfánì akọ̀wé tó jẹ́ ọmọ Asaláyà ọmọ Méṣúlámù sí ilé Jèhófà,+ ó ní: 4 “Lọ bá Hilikáyà+ àlùfáà àgbà, ní kó gba gbogbo owó tí wọ́n mú wá sí ilé Jèhófà+ jọ, èyí tí àwọn aṣọ́nà gbà lọ́wọ́ àwọn èèyàn náà.+ 5 Ní kí wọ́n kó o fún àwọn tí wọ́n yàn láti máa bójú tó iṣẹ́ ilé Jèhófà, àwọn yìí ló máa fún àwọn tó ń ṣiṣẹ́ nínú ilé Jèhófà láti tún àwọn ibi tó bà jẹ́* lára ilé náà ṣe,+ 6 ìyẹn àwọn oníṣẹ́ ọnà àti àwọn kọ́lékọ́lé àti àwọn mọlémọlé; owó yìí ni kí wọ́n fi ra àwọn ẹ̀là gẹdú àti àwọn òkúta gbígbẹ́ tí wọ́n á fi tún ilé náà ṣe.+ 7 Àmọ́, a ò ní sọ pé kí wọ́n ṣe ìṣírò owó tí wọ́n fún wọn, torí pé wọ́n ṣeé fọkàn tán.”+
8 Lẹ́yìn náà, Hilikáyà àlùfáà àgbà sọ fún Ṣáfánì akọ̀wé+ pé: “Mo ti rí ìwé Òfin+ ní ilé Jèhófà.” Torí náà, Hilikáyà fún Ṣáfánì ní ìwé náà, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í kà á.+ 9 Lẹ́yìn náà, Ṣáfánì akọ̀wé lọ sọ́dọ̀ ọba, ó sì sọ fún un pé: “Àwọn ìránṣẹ́ rẹ ti kó owó tí wọ́n rí nínú ilé náà,* wọ́n sì ti kó o fún àwọn tí wọ́n yàn láti máa bójú tó iṣẹ́ ilé Jèhófà.”+ 10 Ṣáfánì akọ̀wé tún sọ fún ọba pé: “Ìwé kan+ wà tí àlùfáà Hilikáyà fún mi.” Ṣáfánì sì bẹ̀rẹ̀ sí í kà á níwájú ọba.
11 Gbàrà tí ọba gbọ́ àwọn ọ̀rọ̀ inú ìwé Òfin náà, ó fa aṣọ rẹ̀ ya.+ 12 Ọba wá pa àṣẹ yìí fún àlùfáà Hilikáyà, Áhíkámù+ ọmọ Ṣáfánì, Ákíbórì ọmọ Mikáyà, Ṣáfánì akọ̀wé àti Ásáyà ìránṣẹ́ ọba pé: 13 “Ẹ lọ wádìí lọ́dọ̀ Jèhófà nítorí tèmi àti nítorí àwọn èèyàn yìí àti nítorí gbogbo Júdà nípa àwọn ọ̀rọ̀ inú ìwé tí a rí yìí; torí ìbínú Jèhófà tó ń jó bí iná lórí wa kò kéré,+ nítorí àwọn baba ńlá wa kò tẹ̀ lé àwọn ọ̀rọ̀ inú ìwé yìí láti ṣe gbogbo ohun tó wà lákọsílẹ̀ fún wa.”
14 Torí náà, àlùfáà Hilikáyà, Áhíkámù, Ákíbórì, Ṣáfánì àti Ásáyà lọ sọ́dọ̀ wòlíì obìnrin+ tó ń jẹ́ Húlídà. Òun ni ìyàwó Ṣálúmù ọmọ Tíkífà ọmọ Háhásì, ẹni tó ń bójú tó ibi tí wọ́n ń kó aṣọ sí. Ó ń gbé ní Apá Kejì Jerúsálẹ́mù; wọ́n sì bá a sọ̀rọ̀ níbẹ̀.+ 15 Ó sọ fún wọn pé: “Ohun tí Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì sọ nìyí, ‘Ẹ sọ fún ọkùnrin tó rán yín wá sọ́dọ̀ mi pé: 16 “Ohun tí Jèhófà sọ nìyí, ‘Màá mú àjálù bá ibí yìí àti àwọn tó ń gbé ibẹ̀, gbogbo ohun tó wà nínú ìwé tí ọba Júdà kà ni màá ṣe.+ 17 Nítorí pé wọ́n ti fi mí sílẹ̀, wọ́n sì ń mú ẹbọ rú èéfín sí àwọn ọlọ́run míì+ láti fi gbogbo iṣẹ́ ọwọ́ wọn mú mi bínú,+ ìbínú mi máa bẹ̀rẹ̀ sí í jó bí iná lórí ibí yìí, kò sì ní ṣeé pa.’”+ 18 Àmọ́, ní ti ọba Júdà tó rán yín pé kí ẹ lọ wádìí lọ́dọ̀ Jèhófà, ẹ sọ fún un pé, “Ohun tí Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì sọ nìyí: ‘Ní ti àwọn ọ̀rọ̀ tí o gbọ́, 19 nítorí pé ọlọ́kàn tútù ni ọ́* tí o sì rẹ ara rẹ sílẹ̀+ níwájú Jèhófà bí o ṣe gbọ́ ohun tí mo sọ pé màá ṣe sí ibí yìí àti sí àwọn tó ń gbé ibẹ̀, pé wọ́n á di ohun àríbẹ̀rù àti ẹni ègún, tí o sì fa aṣọ rẹ ya,+ tí ò ń sunkún níwájú mi, èmi náà ti gbọ́ ohun tí o sọ, ni Jèhófà wí. 20 Ìdí nìyẹn tí màá fi kó ọ jọ sọ́dọ̀ àwọn baba ńlá rẹ,* a ó tẹ́ ọ sínú sàréè rẹ ní àlàáfíà, ojú rẹ ò ní rí gbogbo àjálù tí màá mú bá ibí yìí.’”’” Lẹ́yìn náà, wọ́n mú èsì náà wá fún ọba.
23 Nígbà náà, ọba ránṣẹ́, wọ́n sì pe gbogbo àwọn àgbààgbà Júdà àti Jerúsálẹ́mù jọ.+ 2 Lẹ́yìn náà, ọba lọ sí ilé Jèhófà pẹ̀lú gbogbo èèyàn Júdà, gbogbo àwọn tó ń gbé Jerúsálẹ́mù, àwọn àlùfáà àti àwọn wòlíì, ìyẹn gbogbo àwọn èèyàn náà, látorí ẹni kékeré dórí ẹni ńlá. Ó ka gbogbo ọ̀rọ̀ inú ìwé+ májẹ̀mú+ tí wọ́n rí ní ilé Jèhófà sí wọn létí.+ 3 Ọba dúró lẹ́gbẹ̀ẹ́ òpó, ó sì dá májẹ̀mú* níwájú Jèhófà+ pé gbogbo ọkàn àti gbogbo ara* ni òun á máa fi tẹ̀ lé Jèhófà, òun á sì máa pa àwọn àṣẹ rẹ̀ mọ́ àti àwọn ìránnilétí rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ìlànà rẹ̀, láti máa ṣe ohun tí májẹ̀mú tí a kọ sínú ìwé yìí sọ. Gbogbo àwọn èèyàn náà sì fara mọ́ májẹ̀mú náà.+
4 Ọba wá pàṣẹ fún Hilikáyà+ àlùfáà àgbà àti àwọn àlùfáà yòókù àti àwọn aṣọ́nà pé kí wọ́n kó gbogbo nǹkan èlò tí àwọn èèyàn ṣe fún Báálì àti fún òpó òrìṣà*+ àti fún gbogbo ọmọ ogun ọ̀run jáde nínú tẹ́ńpìlì Jèhófà. Lẹ́yìn náà, ó dáná sun wọ́n ní ìta Jerúsálẹ́mù lórí ilẹ̀ onípele tó wà ní Kídírónì, ó sì kó eérú wọn lọ sí Bẹ́tẹ́lì.+ 5 Ó lé àwọn àlùfáà ọlọ́run ilẹ̀ àjèjì kúrò lẹ́nu iṣẹ́, àwọn tí ọba Júdà yàn láti máa mú ẹbọ rú èéfín lórí àwọn ibi gíga ní àwọn ìlú Júdà àti ní àyíká Jerúsálẹ́mù títí kan àwọn tó ń mú ẹbọ rú èéfín sí Báálì, sí oòrùn àti sí òṣùpá àti sí àwọn àgbájọ ìràwọ̀ sódíákì àti sí gbogbo ọmọ ogun ọ̀run.+ 6 Ó gbé òpó òrìṣà*+ jáde kúrò ní ilé Jèhófà lọ sí ẹ̀yìn Jerúsálẹ́mù, sí Àfonífojì Kídírónì, ó dáná sun ún+ ní Àfonífojì Kídírónì, ó lọ̀ ọ́ kúnná, ó sì fọ́n eruku rẹ̀ sórí sàréè àwọn èèyàn ìlú náà.+ 7 Ó tún wó àwọn ilé aṣẹ́wó ọkùnrin+ tó wà ní tẹ́ńpìlì, èyí tó wà nínú ilé Jèhófà àti ibi tí àwọn obìnrin ti ń hun aṣọ àgọ́ fún ojúbọ òpó òrìṣà.*
8 Lẹ́yìn náà, ó kó gbogbo àwọn àlùfáà jáde kúrò ní àwọn ìlú Júdà, ó sì sọ àwọn ibi gíga tí àwọn àlùfáà ti ń mú ẹbọ rú èéfín di ibi tí kò ṣeé lò fún ìjọsìn, láti Gébà+ títí dé Bíá-ṣébà.+ Ó tún wó àwọn ibi gíga ẹnubodè tó wà ní ibi àtiwọ ẹnubodè Jóṣúà olórí ìlú náà, èyí tó wà lápá òsì tí èèyàn bá wọ ẹnubodè ìlú náà. 9 Àwọn àlùfáà ibi gíga kò ṣiṣẹ́ níbi pẹpẹ Jèhófà tó wà ní Jerúsálẹ́mù,+ àmọ́ wọ́n máa ń jẹ búrẹ́dì aláìwú pẹ̀lú àwọn arákùnrin wọn. 10 Ó tún sọ Tófétì+ tó wà ní Àfonífojì Àwọn Ọmọ Hínómù*+ di ibi tí kò ṣeé lò fún ìjọsìn, kí ẹnikẹ́ni má bàa sun ọmọkùnrin rẹ̀ tàbí ọmọbìnrin rẹ̀ nínú iná sí Mólékì.+ 11 Kò fàyè gba àwọn ẹṣin tí àwọn ọba Júdà yà sọ́tọ̀ fún oòrùn láti máa gba yàrá* Natani-mélékì òṣìṣẹ́ ààfin wọnú ilé Jèhófà, yàrá náà wà níbi àwọn ọ̀nà olórùlé; ó sì dáná sun àwọn kẹ̀kẹ́ ẹṣin oòrùn.+ 12 Ọba tún wó àwọn pẹpẹ tí àwọn ọba Júdà mọ sórí òrùlé+ yàrá òkè Áhásì, títí kan àwọn pẹpẹ tí Mánásè mọ sínú àgbàlá méjì ní ilé Jèhófà.+ Ó fọ́ wọn túútúú, ó sì fọ́n eruku wọn sí Àfonífojì Kídírónì. 13 Ọba sọ àwọn ibi gíga tó wà níwájú Jerúsálẹ́mù di ibi tí kò ṣeé lò fún ìjọsìn, èyí tó wà ní gúúsù* Òkè Ìparun,* tí Sólómọ́nì ọba Ísírẹ́lì mọ fún Áṣítórétì abo ọlọ́run ìríra àwọn ọmọ Sídónì; fún Kémóṣì ọlọ́run ìríra Móábù àti fún Mílíkómù+ ọlọ́run ẹ̀gbin àwọn ọmọ Ámónì.+ 14 Ó fọ́ àwọn ọwọ̀n òrìṣà, ó gé àwọn òpó òrìṣà*+ lulẹ̀, ó sì kó egungun àwọn èèyàn sí àyè wọn. 15 Ó tún wó pẹpẹ tó wà ní Bẹ́tẹ́lì, ìyẹn ibi gíga tí Jèróbóámù ọmọ Nébátì kọ́, tó mú kí Ísírẹ́lì ṣẹ̀.+ Lẹ́yìn tó wó pẹpẹ yẹn àti ibi gíga náà, ó dáná sun ibi gíga náà, ó lọ̀ ọ́ kúnná, ó sì sun òpó òrìṣà*+ náà.
16 Nígbà tí Jòsáyà yíjú pa dà, tó sì rí àwọn sàréè tó wà lórí òkè, ó ní kí wọ́n kó àwọn egungun kúrò nínú àwọn sàréè náà, kí wọ́n sì sun wọ́n lórí pẹpẹ náà, kí ó lè sọ ọ́ di ibi tí kò ṣeé lò fún ìjọsìn, gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ Jèhófà tí èèyàn Ọlọ́run tòótọ́ kéde, nígbà tó sọ tẹ́lẹ̀ pé àwọn nǹkan yìí máa ṣẹlẹ̀.+ 17 Lẹ́yìn náà, ó sọ pé: “Èwo ni òkúta sàréè tí mò ń wò níbẹ̀ yẹn?” Àwọn èèyàn ìlú náà bá sọ fún un pé: “Sàréè èèyàn Ọlọ́run tòótọ́ tó wá láti Júdà+ ni, ẹni tó sọ àsọtẹ́lẹ̀ àwọn ohun tí o ṣe sí pẹpẹ tó wà ní Bẹ́tẹ́lì.” 18 Nítorí náà, ó sọ pé: “Kí ẹnikẹ́ni má fọwọ́ kan egungun rẹ̀, ẹ fi sílẹ̀ bó ṣe wà.” Torí náà, wọn ò fọwọ́ kan egungun rẹ̀, bẹ́ẹ̀ sì ni wọ́n ò fọwọ́ kan egungun wòlíì tó wá láti Samáríà.+
19 Jòsáyà tún mú gbogbo àwọn ilé ìjọsìn tó wà lórí àwọn ibi gíga kúrò ní àwọn ìlú Samáríà,+ èyí tí àwọn ọba Ísírẹ́lì kọ́ láti mú Ọlọ́run bínú, ohun tó ṣe ní Bẹ́tẹ́lì ló ṣe sí àwọn náà.+ 20 Torí náà, ó fi gbogbo àlùfáà àwọn ibi gíga tó wà níbẹ̀ rúbọ lórí àwọn pẹpẹ náà, ó sì sun egungun àwọn èèyàn lórí wọn.+ Lẹ́yìn náà, ó pa dà sí Jerúsálẹ́mù.
21 Ọba wá pàṣẹ fún gbogbo àwọn èèyàn náà pé: “Ẹ ṣe Ìrékọjá+ sí Jèhófà Ọlọ́run yín gẹ́gẹ́ bó ṣe wà lákọsílẹ̀ nínú ìwé májẹ̀mú yìí.”+ 22 Kò sí Ìrékọjá tí wọ́n ṣe tó dà bí èyí láti ìgbà tí àwọn onídàájọ́ ti ń ṣe ìdájọ́ Ísírẹ́lì tàbí ní gbogbo ìgbà tí àwọn ọba Ísírẹ́lì àti àwọn ọba Júdà ti ń jọba.+ 23 Àmọ́ ní ọdún kejìdínlógún Ọba Jòsáyà, wọ́n ṣe Ìrékọjá yìí fún Jèhófà ní Jerúsálẹ́mù.
24 Jòsáyà tún gbá àwọn abẹ́mìílò dà nù àti àwọn woṣẹ́woṣẹ́,+ àwọn ère tẹ́ráfímù,*+ àwọn òrìṣà ẹ̀gbin* pẹ̀lú gbogbo ohun ìríra tó fara hàn ní ilẹ̀ Júdà àti ní Jerúsálẹ́mù, kí ó lè mú àwọn ọ̀rọ̀ Òfin+ tó wà lákọsílẹ̀ nínú ìwé tí àlùfáà Hilikáyà rí ní ilé Jèhófà ṣẹ.+ 25 Ṣáájú rẹ̀, kò sí ọba kankan tó dà bíi rẹ̀, tó fi gbogbo ọkàn rẹ̀, gbogbo ara*+ rẹ̀ àti gbogbo okun rẹ̀ pa dà sọ́dọ̀ Jèhófà, bí gbogbo Òfin Mósè ṣe sọ; bẹ́ẹ̀ ni kò sí ẹni tó jọba lẹ́yìn rẹ̀ tó dà bíi rẹ̀.
26 Síbẹ̀, Jèhófà kò dẹwọ́ ìbínú rẹ̀ tó ń jó bí iná lórí Júdà nítorí gbogbo ohun búburú tí Mánásè ti ṣe láti mú un bínú.+ 27 Jèhófà sọ pé: “Màá mú Júdà kúrò níwájú mi,+ bí mo ṣe mú Ísírẹ́lì kúrò;+ màá kọ Jerúsálẹ́mù sílẹ̀, ìlú tí mo yàn àti ilé tí mo sọ nípa rẹ̀ pé, ‘Orúkọ mi yóò máa wà níbẹ̀.’”+
28 Ní ti ìyókù ìtàn Jòsáyà, gbogbo ohun tí ó ṣe, ǹjẹ́ kò wà lákọsílẹ̀ nínú ìwé ìtàn ìgbà àwọn ọba Júdà? 29 Nígbà ayé rẹ̀, Fáráò Nẹ́kò ọba Íjíbítì wá bá ọba Ásíríà lẹ́gbẹ̀ẹ́ odò Yúfírétì, Ọba Jòsáyà sì jáde lọ kò ó lójú; àmọ́ nígbà tí Nẹ́kò rí i, ó pa á ní Mẹ́gídò.+ 30 Nítorí náà, àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ fi kẹ̀kẹ́ ẹṣin gbé òkú rẹ̀ láti Mẹ́gídò wá sí Jerúsálẹ́mù, wọ́n sì sin ín sí sàréè rẹ̀. Lẹ́yìn náà, àwọn èèyàn ilẹ̀ náà mú Jèhóáhásì ọmọ Jòsáyà, wọ́n fòróró yàn án, wọ́n sì fi í jọba ní ipò bàbá rẹ̀.+
31 Ẹni ọdún mẹ́tàlélógún (23) ni Jèhóáhásì+ nígbà tó jọba, oṣù mẹ́ta ló sì fi ṣàkóso ní Jerúsálẹ́mù. Orúkọ ìyá rẹ̀ ni Hámútálì+ ọmọ Jeremáyà láti Líbínà. 32 Ó bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe ohun tó burú ní ojú Jèhófà, gbogbo ohun tí àwọn baba ńlá rẹ̀ ṣe ni òun náà ṣe.+ 33 Fáráò Nẹ́kò+ fi í sínú ẹ̀wọ̀n ní Ríbúlà+ nílẹ̀ Hámátì, kó má bàa jọba lórí Jerúsálẹ́mù mọ́, ó wá bu owó ìtanràn lé ilẹ̀ náà, ọgọ́rùn-ún (100) tálẹ́ńtì* fàdákà àti tálẹ́ńtì wúrà kan.+ 34 Yàtọ̀ síyẹn, Fáráò Nẹ́kò fi Élíákímù ọmọ Jòsáyà jọba ní ipò Jòsáyà bàbá rẹ̀, ó sì yí orúkọ rẹ̀ pa dà sí Jèhóákímù; àmọ́ ó mú Jèhóáhásì wá sí Íjíbítì,+ ibẹ̀ ló sì kú sí nígbẹ̀yìn.+ 35 Jèhóákímù fún Fáráò ní fàdákà àti wúrà náà, àmọ́ ṣe ló bu owó orí lé ilẹ̀ náà, kó lè fún Fáráò ní fàdákà tó béèrè. Ó gba iye fàdákà àti wúrà tí ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn èèyàn ilẹ̀ náà máa san, kó lè fún Fáráò Nẹ́kò.
36 Ẹni ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n (25) ni Jèhóákímù+ nígbà tó jọba, ọdún mọ́kànlá (11) ló sì fi ṣàkóso ní Jerúsálẹ́mù.+ Orúkọ ìyá rẹ̀ ni Sébídà ọmọ Pedáyà láti Rúmà. 37 Ó ń ṣe ohun tó burú ní ojú Jèhófà,+ gbogbo ohun tí àwọn bàbá ńlá rẹ̀ ṣe ni òun náà ṣe.+
24 Nígbà ayé Jèhóákímù, Nebukadinésárì+ ọba Bábílónì wá gbéjà kò ó, Jèhóákímù sì fi ọdún mẹ́ta ṣe ìránṣẹ́ fún un. Àmọ́, ó yí pa dà, ó sì ṣọ̀tẹ̀. 2 Lẹ́yìn náà, Jèhófà bẹ̀rẹ̀ sí í rán àwọn akónilẹ́rù* àwọn ará Kálídíà,+ ti àwọn ará Síríà, ti àwọn ọmọ Móábù àti ti àwọn ọmọ Ámónì sí i. Ó ń rán wọn sí Júdà léraléra láti pa á run, gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ tí Jèhófà+ gbẹnu àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀, wòlíì sọ. 3 Ó dájú pé àṣẹ tí Jèhófà pa ló mú kí èyí ṣẹlẹ̀ sí Júdà, kí ó lè mú wọn kúrò níwájú rẹ̀+ nítorí gbogbo àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tí Mánásè dá+ 4 àti nítorí ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ tí ó ta sílẹ̀,+ torí ó ti fi ẹ̀jẹ̀ àwọn aláìṣẹ̀ kún Jerúsálẹ́mù, Jèhófà kò sì fẹ́ dárí jì wọ́n.+
5 Ní ti ìyókù ìtàn Jèhóákímù àti gbogbo ohun tí ó ṣe, ǹjẹ́ kò wà lákọsílẹ̀ nínú ìwé ìtàn ìgbà àwọn ọba Júdà?+ 6 Níkẹyìn, Jèhóákímù sinmi pẹ̀lú àwọn baba ńlá rẹ̀;+ Jèhóákínì ọmọ rẹ̀ sì jọba ní ipò rẹ̀.
7 Ọba Íjíbítì kò tún jáde kúrò ní ilẹ̀ rẹ̀ mọ́, torí pé ọba Bábílónì ti gba gbogbo ohun tí ọba Íjíbítì ní,+ ìyẹn láti Àfonífojì Íjíbítì+ títí dé odò Yúfírétì.+
8 Ọmọ ọdún méjìdínlógún (18) ni Jèhóákínì+ nígbà tó jọba, oṣù mẹ́ta ló sì fi ṣàkóso ní Jerúsálẹ́mù.+ Orúkọ ìyá rẹ̀ ni Néhúṣítà ọmọ Élínátánì láti Jerúsálẹ́mù. 9 Ó ń ṣe ohun tó burú ní ojú Jèhófà, gbogbo ohun tí bàbá rẹ̀ ṣe ni òun náà ṣe. 10 Lákòókò yẹn, àwọn ìránṣẹ́ Nebukadinésárì ọba Bábílónì wá gbéjà ko Jerúsálẹ́mù, wọ́n sì dó ti ìlú náà.+ 11 Nebukadinésárì ọba Bábílónì wá sí ìlú náà nígbà tí àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ dó tì í.
12 Jèhóákínì ọba Júdà jáde lọ bá ọba Bábílónì,+ òun àti ìyá rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀, àwọn ìjòyè rẹ̀ àti àwọn òṣìṣẹ́ ààfin rẹ̀;+ ọba Bábílónì sì mú un lẹ́rú ní ọdún kẹjọ ìṣàkóso rẹ̀.+ 13 Lẹ́yìn náà, ó kó gbogbo ìṣúra ilé Jèhófà àti ìṣúra ilé* ọba jáde kúrò.+ Gbogbo nǹkan èlò wúrà tí Sólómọ́nì ọba Ísírẹ́lì ṣe sínú tẹ́ńpìlì Jèhófà+ ni ó gé sí wẹ́wẹ́. Èyí ṣẹlẹ̀ bí Jèhófà ṣe sọ tẹ́lẹ̀ gẹ́lẹ́. 14 Ó kó gbogbo Jerúsálẹ́mù lọ sí ìgbèkùn, gbogbo ìjòyè,+ gbogbo jagunjagun tó lákíkanjú àti gbogbo oníṣẹ́ ọnà pẹ̀lú gbogbo oníṣẹ́ irin,*+ ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá (10,000) èèyàn ló kó lọ sí ìgbèkùn. Kò ṣẹ́ ku ẹnì kankan àfi àwọn aláìní ní ilẹ̀ náà.+ 15 Bó ṣe mú Jèhóákínì+ lọ sí ìgbèkùn ní Bábílónì+ nìyẹn; ó tún mú ìyá ọba, àwọn ìyàwó ọba, àwọn òṣìṣẹ́ ààfin àti àwọn aṣáájú ilẹ̀ náà, ó sì kó wọn ní ìgbèkùn láti Jerúsálẹ́mù lọ sí Bábílónì. 16 Ọba Bábílónì tún kó gbogbo àwọn jagunjagun lọ sí ìgbèkùn ní Bábílónì, ẹgbẹ̀rún méje (7,000) ni wọ́n àti ẹgbẹ̀rún kan (1,000) àwọn oníṣẹ́ ọnà àti àwọn oníṣẹ́ irin,* alágbára ni gbogbo wọn, wọ́n sì ti kọ́ iṣẹ́ ogun. 17 Ọba Bábílónì fi Matanáyà àbúrò bàbá Jèhóákínì+ jọba ní ipò rẹ̀, ó sì yí orúkọ rẹ̀ pa dà sí Sedekáyà.+
18 Ẹni ọdún mọ́kànlélógún (21) ni Sedekáyà nígbà tó jọba, ọdún mọ́kànlá (11) ló sì fi ṣàkóso ní Jerúsálẹ́mù. Orúkọ ìyá rẹ̀ ni Hámútálì+ ọmọ Jeremáyà láti Líbínà. 19 Ó ń ṣe ohun tó burú ní ojú Jèhófà, gbogbo ohun tí Jèhóákímù ṣe ni òun náà ṣe.+ 20 Ìbínú Jèhófà ló mú kí àwọn nǹkan yìí ṣẹlẹ̀ ní Jerúsálẹ́mù àti ní Júdà, títí ó fi gbá wọn dà nù kúrò níwájú rẹ̀.+ Sedekáyà sì ṣọ̀tẹ̀ sí ọba Bábílónì.+
25 Ní ọdún kẹsàn-án ìjọba Sedekáyà, ní oṣù kẹwàá, ní ọjọ́ kẹwàá oṣù náà, Nebukadinésárì+ ọba Bábílónì dé pẹ̀lú gbogbo ọmọ ogun rẹ̀ láti gbéjà ko Jerúsálẹ́mù.+ Ó dó tì í, ó mọ òkìtì yí i ká,+ 2 wọ́n sì dó ti ìlú náà títí di ọdún kọkànlá ìṣàkóso Ọba Sedekáyà. 3 Ní ọjọ́ kẹsàn-án oṣù kẹrin, ìyàn mú gan-an+ ní ìlú náà, kò sì sí oúnjẹ kankan tí àwọn èèyàn ilẹ̀ náà máa jẹ.+ 4 Wọ́n fọ́ ògiri ìlú náà wọlé,+ gbogbo ọmọ ogun sì sá gba ẹnubodè tó wà láàárín ògiri oníbejì nítòsí ọgbà ọba lóru, lákòókò yìí, àwọn ará Kálídíà yí ìlú náà ká; ọba sì sá gba ọ̀nà Árábà.+ 5 Àmọ́ àwọn ọmọ ogun Kálídíà lé ọba, wọ́n sì bá a ní aṣálẹ̀ tó wà ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Jẹ́ríkò, gbogbo ọmọ ogun rẹ̀ sì tú ká kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀. 6 Lẹ́yìn náà, wọ́n gbá ọba mú,+ wọ́n mú un wá sọ́dọ̀ ọba Bábílónì ní Ríbúlà, wọ́n sì dá a lẹ́jọ́. 7 Wọ́n pa àwọn ọmọ Sedekáyà níṣojú rẹ̀; Nebukadinésárì wá fọ́ ojú Sedekáyà, ó fi ṣẹkẹ́ṣẹkẹ̀ bàbà dè é, ó sì mú un wá sí Bábílónì.+
8 Ní oṣù karùn-ún, ní ọjọ́ keje oṣù náà, ìyẹn ní ọdún kọkàndínlógún Nebukadinésárì ọba Bábílónì, Nebusarádánì+ olórí ẹ̀ṣọ́, ìránṣẹ́ ọba Bábílónì, wá sí Jerúsálẹ́mù.+ 9 Ó dáná sun ilé Jèhófà+ àti ilé* ọba+ pẹ̀lú gbogbo ilé tó wà ní Jerúsálẹ́mù;+ ó tún sun ilé gbogbo àwọn ẹni ńlá.+ 10 Gbogbo ògiri tó yí Jerúsálẹ́mù ká ni gbogbo àwọn ọmọ ogun Kálídíà tó wà pẹ̀lú olórí ẹ̀ṣọ́ wó lulẹ̀.+ 11 Nebusarádánì olórí ẹ̀ṣọ́ kó àwọn tó ṣẹ́ kù lára àwọn èèyàn tó wà ní ìlú náà lọ sí ìgbèkùn ní Bábílónì àti àwọn tó sá wá sọ́dọ̀ ọba Bábílónì pẹ̀lú gbogbo àwọn tí ó kù.+ 12 Àmọ́ olórí ẹ̀ṣọ́ fi lára àwọn aláìní sílẹ̀ ní ilẹ̀ náà kí wọ́n lè máa rẹ́ ọwọ́ àjàrà, kí wọ́n sì máa ṣe lébìrà àpàpàǹdodo.+ 13 Àwọn ará Kálídíà fọ́ àwọn òpó bàbà+ ilé Jèhófà àti àwọn kẹ̀kẹ́ ẹrù+ àti Òkun bàbà+ tó wà ní ilé Jèhófà sí wẹ́wẹ́, wọ́n sì kó àwọn bàbà náà lọ sí Bábílónì.+ 14 Wọ́n tún kó àwọn garawa, àwọn ṣọ́bìrì, àwọn ohun tí wọ́n fi ń pa fìtílà, àwọn ife àti gbogbo nǹkan èlò bàbà tí wọ́n ń lò nínú tẹ́ńpìlì. 15 Olórí ẹ̀ṣọ́ kó àwọn ìkóná àti àwọn abọ́ tí wọ́n fi ojúlówó wúrà+ ṣe àti àwọn tí wọ́n fi ojúlówó fàdákà+ ṣe. 16 Ní ti àwọn òpó méjèèjì àti Òkun pẹ̀lú àwọn kẹ̀kẹ́ ẹrù tí Sólómọ́nì ṣe fún ilé Jèhófà, bàbà tó wà lára gbogbo àwọn nǹkan èlò yìí kọjá wíwọ̀n.+ 17 Gíga ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn òpó náà jẹ́ ìgbọ̀nwọ́* méjìdínlógún (18),+ bàbà ni wọ́n fi ṣe ọpọ́n tó wà lórí rẹ̀; gíga ọpọ́n náà sì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́ta, bàbà ni wọ́n fi ṣe àwọ̀n àti àwọn pómégíránétì tó yí ọpọ́n náà ká.+ Òpó kejì àti àwọ̀n rẹ̀ sì dà bíi ti àkọ́kọ́.
18 Olórí ẹ̀ṣọ́ tún mú Seráyà+ olórí àlùfáà àti Sefanáyà+ àlùfáà kejì pẹ̀lú àwọn aṣọ́nà mẹ́ta.+ 19 Ó mú òṣìṣẹ́ ààfin kan tó jẹ́ kọmíṣọ́nnà lórí àwọn ọmọ ogun láti inú ìlú náà àti ọkùnrin márùn-ún tó rí nínú ìlú náà tí wọ́n sún mọ́ ọba àti akọ̀wé olórí àwọn ọmọ ogun, tó máa ń pe àwọn èèyàn ilẹ̀ náà jọ àti ọgọ́ta (60) ọkùnrin lára àwọn èèyàn ilẹ̀ náà, tó tún rí nínú ìlú náà. 20 Nebusarádánì+ olórí ẹ̀ṣọ́ mú wọn, ó sì kó wọn wá sọ́dọ̀ ọba Bábílónì ní Ríbúlà.+ 21 Ọba Bábílónì ṣá wọn balẹ̀, ó sì pa wọ́n ní Ríbúlà ní ilẹ̀ Hámátì.+ Bí Júdà ṣe lọ sí ìgbèkùn láti ilẹ̀ rẹ̀ nìyẹn.+
22 Nebukadinésárì ọba Bábílónì yan Gẹdaláyà+ ọmọ Áhíkámù+ ọmọ Ṣáfánì+ ṣe olórí àwọn èèyàn tí ó fi sílẹ̀ ní ilẹ̀ Júdà.+ 23 Nígbà tí gbogbo olórí àwọn ọmọ ogun àti àwọn ọkùnrin wọn gbọ́ pé ọba Bábílónì ti yan Gẹdaláyà, lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, wọ́n wá sọ́dọ̀ Gẹdaláyà ní Mísípà. Àwọn ni Íṣímáẹ́lì ọmọ Netanáyà, Jóhánánì ọmọ Káréà, Seráyà ọmọ Táńhúmétì ará Nétófà àti Jaasanáyà ọmọ ará Máákátì pẹ̀lú àwọn ọkùnrin wọn.+ 24 Gẹdaláyà búra fún wọn àti fún àwọn ọkùnrin wọn, ó sì sọ pé: “Ẹ má bẹ̀rù láti sin àwọn ará Kálídíà. Ẹ máa gbé ilẹ̀ yìí, kí ẹ máa sin ọba Bábílónì, nǹkan á sì máa lọ dáadáa fún yín.”+
25 Ní oṣù keje, Íṣímáẹ́lì+ ọmọ Netanáyà ọmọ Élíṣámà, tó wá láti ìdílé ọba,* wá pẹ̀lú àwọn ọkùnrin mẹ́wàá míì, wọ́n ṣá Gẹdaláyà balẹ̀, ó sì kú, òun àti àwọn Júù àti àwọn ará Kálídíà tó wà pẹ̀lú rẹ̀ ní Mísípà.+ 26 Lẹ́yìn ìyẹn, gbogbo àwọn èèyàn náà dìde, látorí ẹni kékeré dórí ẹni ńlá, títí kan àwọn olórí ọmọ ogun, wọ́n sì lọ sí Íjíbítì,+ nítorí ẹ̀rù àwọn ará Kálídíà ń bà wọ́n.+
27 Ní ọdún kẹtàdínlógójì tí Jèhóákínì+ ọba Júdà ti wà ní ìgbèkùn, ní oṣù kejìlá, ní ọjọ́ kẹtàdínlọ́gbọ̀n oṣù náà, Efili-méródákì ọba Bábílónì, ní ọdún tó jọba, dá Jèhóákínì ọba Júdà sílẹ̀* lẹ́wọ̀n.+ 28 Ó bá a sọ̀rọ̀ pẹ̀lẹ́, ó sì gbé ìtẹ́ rẹ̀ ga ju ìtẹ́ àwọn ọba yòókù tó wà pẹ̀lú rẹ̀ ní Bábílónì. 29 Torí náà, Jèhóákínì bọ́ ẹ̀wù ẹ̀wọ̀n rẹ̀, iwájú ọba ló sì ti ń jẹun déédéé ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀. 30 Ó ń rí oúnjẹ gbà déédéé látọ̀dọ̀ ọba, lójoojúmọ́ ayé rẹ̀.
Ó túmọ̀ sí “Jèhófà Ni Ọlọ́run Mi.”
Tàbí “jẹ́ kí ọkàn mi àti ọkàn.”
Tàbí “ọkàn.”
Ìyẹn, àbúrò Ahasáyà.
Tàbí “sánmà.”
Tàbí “ọkàn rẹ.”
“Àwọn ọmọ wòlíì” ṣeé ṣe kó máa tọ́ka sí ilé ẹ̀kọ́ tí àwọn wòlíì ti ń gba ìtọ́ni tàbí ẹgbẹ́ àwọn wòlíì.
Tàbí “ọkàn rẹ.”
Tàbí “ọkàn rẹ.”
Tàbí “apá.”
Tàbí “sánmà.”
Tàbí “ìjì.”
Tàbí kó jẹ́, “ń ba oyún jẹ́.”
Tàbí kó jẹ́, “kò sì ní ba oyún jẹ́.”
Tàbí “owó òde.”
Tàbí “tó jẹ́ ìránṣẹ́ Èlíjà.”
Ní Héb., “Kí ló wà láàárín èmi àti ìwọ?”
Ní Héb., “ẹni tí mo dúró níwájú rẹ̀.”
Tàbí “olórin kan.”
Ní Héb., “ọwọ́.”
Tàbí “tó ń de àmùrè.”
Tàbí “ìṣà ẹlẹ́nu ṣọọrọ.”
Tàbí “ìkòkò.”
Tàbí “di kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ní gàárì.”
Tàbí “ọkàn rẹ̀ ló gbọgbẹ́.”
Tàbí “tí ọkàn rẹ.”
Tàbí “rí ìgbàlà.”
Tàbí “àìsàn kan ń ṣe é nínú awọ ara rẹ̀.”
Ó ṣeé ṣe kó máa tọ́ka sí Náámánì.
Tálẹ́ńtì kan jẹ́ kìlógíráàmù 34.2. Wo Àfikún B14.
Tàbí “tẹ.”
Ní Héb., “ibùdó rẹ̀.”
Ní Héb., “ìbùkún.”
Ní Héb., “tí mo dúró níwájú rẹ̀.”
Ọ̀rọ̀ yìí ní Hébérù ń tọ́ka sí ìbaaka.
Tàbí “tẹ́ńpìlì.”
Ibì kan ní Samáríà tó ṣeé ṣe kó jẹ́ òkè tàbí ibi tó láàbò.
Tàbí “kì í ṣe ẹ̀ẹ̀kan tàbí ẹ̀ẹ̀mejì.”
Ní Héb., “mú kí ọkàn ọba Síríà ru.”
Tàbí “òjíṣẹ́.”
Tàbí “akónilẹ́rù.”
Ní Héb., “ibùdó.”
Káàbù kan jẹ́ Lítà 1.22. Wo Àfikún B14.
Ní Héb., “aṣọ àpò ìdọ̀họ.”
Tàbí “sísàlẹ̀, lé awọ ara.”
Síà kan jẹ́ Lítà 7.33. Wo Àfikún B14.
Ṣékélì kan jẹ́ gíráàmù 11.4. Wo Àfikún B14.
Tàbí “ọjà.”
Ní Héb., “ọ̀rọ̀.”
Tàbí “ọkàn.”
Ní Héb., “ọ̀rọ̀.”
Tàbí “tí ó mú kó sọ jí.”
Tàbí “dà á bo ojú rẹ̀.”
Ní Héb., “òun á fún Dáfídì àti àwọn ọmọ rẹ̀ ní fìtílà.”
Ní Héb., “ọmọ.”
Tàbí “ó ń ṣàìsàn.”
Ìyẹn, ohun tí a fi amọ̀ ṣe tó dà bí ìgò ńlá.
Ní Héb., “ẹnikẹ́ni tó ń tọ̀ sára ògiri.” Ọ̀rọ̀ Hébérù tí wọ́n fi ń pẹ̀gàn àwọn ọkùnrin.
Tàbí “ọkàn yín.”
Ní Héb., “ọmọ.”
Ní Héb., “ọrun.”
Ní Héb., “àwọn kẹ̀kẹ́ ẹṣin tí ọ̀wọ́ ẹṣin ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ń fà.”
Tàbí “tọ́ lẹ́ẹ̀dì.”
Tàbí “wíńdò.”
Ní Héb., “àwọn olùtọ́jú Áhábù.”
Tàbí “dúró ṣánṣán.”
Ní Héb., “ilé.”
Tàbí “Olódodo ni yín.”
Ní Héb., “tó máa já bọ́ sílẹ̀.”
Ó jọ pé ibì kan tí wọ́n ti ń so àgùntàn kí wọ́n lè rẹ́ irun wọn ni.
Tàbí “ìyáàfin.”
Tàbí “súre fún un.”
Ní Héb., “dúró ṣánṣán.”
Tàbí “kí o sì rí ìtara mi fún Jèhófà.”
Ní Héb., “Ẹ ya àpéjọ ọ̀wọ̀ sí mímọ́.”
Tàbí “tẹ́ńpìlì.”
Tàbí “ọkàn.”
Ní Héb., “àwọn sárésáré.”
Ní Héb., “ìlú,” ó ṣeé ṣe kó jẹ́ ilé tí wọ́n kọ́ bí ibi tó láàbò.
Tàbí “dín.”
Ní Héb., “Ọjọ́.”
Ní Héb., “gbogbo èso ìjọba.”
Ní Héb., “àwọn sárésáré.”
Tàbí “dá májẹ̀mú.”
Tàbí “ààfin.”
Ní Héb., “nígbà tó bá jáde àti nígbà tó bá wọlé.”
Tàbí “apata ribiti.”
Tàbí “dáyádémà.”
Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ ìwé tí Òfin Ọlọ́run wà nínú rẹ̀.
Tàbí “ààfin.”
Tàbí “tẹ́ńpìlì.”
Tàbí “ààfin.”
Ní Héb., “fi idà pa.”
Tàbí “ọkàn.”
Tàbí “ojúlùmọ̀ wọn.”
Tàbí “sán.”
Tàbí “kó owó náà sínú àwọn àpò.” Ní Héb., “di owó náà.”
Ní Héb., “Hásáélì dojú kọ Jerúsálẹ́mù láti gbéjà kò ó.”
Tàbí “ààfin.”
Tàbí “Bẹti-mílò.”
Tàbí “tu Jèhófà lójú.”
Ìyẹn, ní àlàáfíà àti ààbò.
Ní Héb., “Inú rẹ̀ ló ti ń rìn.”
Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.
Ní Héb., “Inú ẹ̀ṣẹ̀ náà ló ti ń rìn.”
Ìyẹn, Jèróbóámù Kejì.
Tàbí “wíńdò.”
Tàbí “ìgbàlà.”
Tàbí “ìgbàlà.”
Tàbí “borí Síríà.”
Tàbí “akónilẹ́rù.”
Ní Héb., “nígbà tí ọdún ń wọlé dé,” ó ṣeé ṣe kó jẹ́ ìgbà ìrúwé.
Tàbí “akónilẹ́rù.”
Tàbí “ṣẹ́gun rẹ̀.”
Tàbí “jẹ́ ká wojú ara wa.”
Tàbí “ààfin.”
Ní Héb., “àgọ́.”
Nǹkan bíi mítà 178 (ẹsẹ̀ bàtà 584). Wo Àfikún B14.
Tàbí “ààfin.”
Ìyẹn, Jèróbóámù Kejì.
Ó túmọ̀ sí “Jèhófà Ti Ṣèrànwọ́.” Wọ́n pè é ní Ùsáyà ní 2Ọb 15:13; 2Kr 26:1-23; Ais 6:1 àti Sek 14:5.
Ìyẹn, Amasááyà bàbá rẹ̀.
Tàbí “àbáwọlé Hámátì.”
Ìyẹn, Òkun Iyọ̀ tàbí Òkun Òkú.
Ìyẹn, Jèróbóámù Kejì.
Ó túmọ̀ sí “Jèhófà Ti Ṣèrànwọ́.” Wọ́n pè é ní Ùsáyà ní 2Ọb 15:13; 2Kr 26:1-23; Ais 6:1 àti Sek 14:5.
Tàbí “ààfin.”
Tálẹ́ńtì kan jẹ́ kìlógíráàmù 34.2. Wo Àfikún B14.
Ṣékélì kan jẹ́ gíráàmù 11.4. Wo Àfikún B14.
Tàbí “ààfin.”
Tàbí “àwọn èèyàn Júdà.”
Tàbí “ààfin.”
Ó túmọ̀ sí “Jèhófà Ń Fúnni Lókun.”
Tàbí “owó òde.”
Tàbí “owó òde.”
Ní Héb., “bẹ̀rù.”
Ìyẹn, ní ibi gbogbo, ì báà jẹ́ ibi tí èèyàn kéréje ń gbé tàbí ọ̀pọ̀ èèyàn.
Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.
Ó ṣeé ṣe kí ọ̀rọ̀ Hébérù yìí ní í ṣe pẹ̀lú ọ̀rọ̀ tí wọ́n ń lò fún “ìgbẹ́,” wọ́n sì máa ń lò ó fún ohun tí wọ́n bá kórìíra.
Ní Héb., “wọ́n mú kí ọrùn wọn le bí ọrùn.”
Tàbí “ère dídà.”
Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.
Ní Héb., “ta ara wọn.”
Tàbí “jọ́sìn.”
Tàbí “àwọn àṣà tó wà nínú ẹ̀sìn.”
Tàbí “jọ́sìn.”
Tàbí “ṣe àwọn ọlọ́run tiwọn.”
Tàbí “àwọn àṣà tó wà nínú ẹ̀sìn.”
Tàbí “àwọn àṣà tó wà nínú ẹ̀sìn.”
Tàbí “bẹ̀rù.”
Tàbí “àwọn àṣà tó wà nínú ẹ̀sìn.”
Ìkékúrú orúkọ Ábíjà.
Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.
Tàbí “Néhúṣítánì.”
Ìyẹn, ní ibi gbogbo, ì báà jẹ́ ibi tí èèyàn kéréje ń gbé tàbí ọ̀pọ̀ èèyàn.
Tálẹ́ńtì kan jẹ́ kìlógíráàmù 34.2. Wo Àfikún B14.
Tàbí “ààfin.”
Ní Héb., “gé.”
Tàbí “olórí ọmọ ogun.”
Tàbí “olórí àwọn òṣìṣẹ́ láàfin.”
Tàbí “olórí agbọ́tí.”
Tàbí “ààfin.”
Ìyẹn, koríko etí omi.
Tàbí “Síríà.”
Ní Héb., “Ẹ wá ìbùkún lọ́dọ̀ mi, kí ẹ sì jáde wá bá mi.”
Tàbí “ààfin.”
Ní Héb., “aṣọ àpò ìdọ̀họ.”
Tàbí “ààfin.”
Ní Héb., “aṣọ àpò ìdọ̀họ.”
Tàbí “èébú.”
Ní Héb., “àwọn ọmọ ti dé ẹnu ilé ọmọ.”
Tàbí “ìránṣẹ́.”
Ní Héb., “ẹ̀mí kan sínú rẹ̀.”
Ní Héb., “ẹ.”
Tàbí kó jẹ́, “láàárín.”
Tàbí “ipa odò Náílì.”
Ní Héb., “ni mo ti ṣe é.”
Tàbí “mọ ọ́n.”
Ìyẹn, Hẹsikáyà.
Tàbí “hóró ọkà tó dà sílẹ̀ tó lalẹ̀ hù.”
Tàbí “tẹ́ńpìlì.”
Ní Héb., “àwọn ọjọ́.”
Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé àwọn àtẹ̀gùn yìí ni wọ́n fi ń ka àkókò bíi ti aago òjìji oòrùn.
Tàbí “fetí sí wọn.”
Tàbí “ààfin.”
Tàbí “ààfin.”
Tàbí “ààfin.”
Tàbí “ààfin.”
Tàbí “òtítọ́.”
Ní Héb., “ní àwọn ọjọ́.”
Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.
Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.
Ó ṣeé ṣe kí ọ̀rọ̀ Hébérù yìí ní í ṣe pẹ̀lú ọ̀rọ̀ tí wọ́n ń lò fún “ìgbẹ́,” wọ́n sì máa ń lò ó fún ohun tí wọ́n bá kórìíra.
Tàbí “okùn tí a fi ń mọ̀ bóyá nǹkan gún régé.”
Tàbí “tó sán.”
Ní Héb., “da owó tí wọ́n rí nínú ilé náà jáde.”
Ní Héb., “ọkàn rẹ rọ̀.”
Àkànlò èdè yìí ni wọ́n fi ń sọ pé èèyàn kú.
Tàbí “tún májẹ̀mú dá.”
Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.
Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.
Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.
Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.
Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀, “Gẹ̀hẹ́nà.”
Tàbí “yàrá ìjẹun.”
Ní Héb., “ọ̀tún.” Ìyẹn, gúúsù, tí èèyàn bá dojú kọ ìlà oòrùn.
Ìyẹn, Òkè Ólífì, pàápàá ìkángun gúúsù tí wọ́n tún ń pè ní Òkè Ìpèníjà.
Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.
Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.
Tàbí “àwọn òrìṣà ìdílé; òrìṣà.”
Ó ṣeé ṣe kí ọ̀rọ̀ Hébérù yìí ní í ṣe pẹ̀lú ọ̀rọ̀ tí wọ́n ń lò fún “ìgbẹ́,” wọ́n sì máa ń lò ó fún ohun tí wọ́n bá kórìíra.
Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.
Tálẹ́ńtì kan jẹ́ kìlógíráàmù 34.2. Wo Àfikún B14.
Tàbí “jàǹdùkú.”
Tàbí “ààfin.”
Tàbí kó jẹ́, “àwọn tó ń kọ́ odi ààbò.”
Tàbí kó jẹ́, “àwọn tó ń kọ́ odi ààbò.”
Tàbí “ààfin.”
Ìgbọ̀nwọ́ kan jẹ́ sẹ̀ǹtímítà 44.5 (ínǹṣì 17.5). Wo Àfikún B14.
Ní Héb., “látinú èso ìjọba náà.”
Ní Héb., “gbé orí Jèhóákínì ọba Júdà sókè.”