SÁMÚẸ́LÌ KÌÍNÍ
1 Ọkùnrin kan wà, ó wá láti ìlú Ramataimu-sófíímù*+ ní agbègbè olókè Éfúrémù,+ orúkọ rẹ̀ ni Ẹlikénà,+ ọmọ Jéróhámù, ọmọ Élíhù, ọmọ Tóhù, ọmọ Súfì, ó jẹ́ ará Éfúrémù. 2 Ó ní ìyàwó méjì, ọ̀kan ń jẹ́ Hánà, èkejì sì ń jẹ́ Pẹ̀nínà. Pẹ̀nínà bí àwọn ọmọ, ṣùgbọ́n Hánà kò bímọ. 3 Lọ́dọọdún, ọkùnrin yẹn máa ń lọ láti ìlú rẹ̀ sí Ṣílò+ láti jọ́sìn,* kó sì rúbọ sí Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun. Ibẹ̀ ni àwọn ọmọkùnrin Élì méjèèjì, Hófínì àti Fíníhásì+ ti ń ṣe iṣẹ́ àlùfáà fún Jèhófà.+
4 Lọ́jọ́ kan tí Ẹlikénà rúbọ, ó pín lára ẹran tó fi rúbọ fún Pẹ̀nínà ìyàwó rẹ̀ àti gbogbo ọmọkùnrin rẹ̀ àti ọmọbìnrin rẹ̀,+ 5 ṣùgbọ́n ó fún Hánà ní ìpín kan tó ṣàrà ọ̀tọ̀, torí pé Hánà ló fẹ́ràn jù, àmọ́ Jèhófà kò tíì fún Hánà ní ọmọ.* 6 Yàtọ̀ síyẹn, orogún rẹ̀ ń pẹ̀gàn rẹ̀ ṣáá kó lè múnú bí i nítorí pé Jèhófà kò tíì fún un ní ọmọ. 7 Ohun tó máa ń ṣe nìyẹn lọ́dọọdún, nígbàkigbà tí Hánà bá lọ sí ilé Jèhófà,+ orogún rẹ̀ máa ń pẹ̀gàn rẹ̀ débi pé ńṣe ló máa ń sunkún, tí kò sì ní jẹun. 8 Àmọ́ Ẹlikénà ọkọ rẹ̀ sọ fún un pé: “Hánà, kí ló ń pa ẹ́ lẹ́kún, kí ló dé tó ò jẹun, kí ló ń bà ẹ́ nínú jẹ́?* Ṣé mi ò sàn ju ọmọkùnrin mẹ́wàá lọ fún ọ ni?”
9 Nígbà náà, Hánà dìde lẹ́yìn tí wọ́n ti parí jíjẹ àti mímu ní Ṣílò. Ní àkókò yẹn, àlùfáà Élì jókòó lórí ìjókòó tó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ òpó ilẹ̀kùn tẹ́ńpìlì*+ Jèhófà. 10 Inú Hánà bà jẹ́* gan-an, ó bẹ̀rẹ̀ sí í gbàdúrà sí Jèhófà,+ ó sì ń sunkún tẹ̀dùntẹ̀dùn. 11 Ó wá jẹ́ ẹ̀jẹ́ yìí pé: “Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun, tí o bá bojú wo ìnira tó dé bá ìránṣẹ́ rẹ, tí o rántí mi, tí o kò gbàgbé ìránṣẹ́ rẹ, tí o sì fún ìránṣẹ́ rẹ ní ọmọ ọkùnrin,+ ṣe ni màá fi fún Jèhófà ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀, abẹ kò sì ní kan orí rẹ̀.”+
12 Ní gbogbo àkókò tó fi ń gbàdúrà níwájú Jèhófà, Élì ń wo ẹnu rẹ̀. 13 Hánà ń gbàdúrà nínú ọkàn rẹ̀, ètè rẹ̀ nìkan ló ń mì, a kò sì gbọ́ ohùn rẹ̀. Torí náà, Élì rò pé ó mutí yó ni. 14 Élì sọ fún un pé: “Ìgbà wo ni ọtí máa tó dá lójú rẹ? Má mutí mọ́.” 15 Ni Hánà bá dáhùn pé: “Kò rí bẹ́ẹ̀, olúwa mi! Ìdààmú ńlá ló bá mi;* kì í ṣe pé mo mu wáìnì tàbí ọtí kankan, ohun tó wà lọ́kàn mi ni mò ń tú jáde níwájú Jèhófà.+ 16 Má rò pé obìnrin tí kò ní láárí ni ìránṣẹ́ rẹ, àdúrà ni mò ń gbà títí di báyìí nítorí ìrora àti ìdààmú ńlá tó dé bá mi.” 17 Ni Élì bá dáhùn pé: “Máa lọ ní àlàáfíà, kí Ọlọ́run Ísírẹ́lì sì fún ọ ní ohun tí o béèrè lọ́wọ́ rẹ̀.”+ 18 Hánà fèsì pé: “Kí ìránṣẹ́ rẹ rí ojú rere lọ́dọ̀ rẹ.” Obìnrin náà sì bá tirẹ̀ lọ, ó jẹun, kò sì kárí sọ mọ́.
19 Lẹ́yìn náà, wọ́n dìde ní àárọ̀ kùtù, wọ́n forí balẹ̀ níwájú Jèhófà, wọ́n sì pa dà sí ilé wọn ní Rámà.+ Ẹlikénà ní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú Hánà ìyàwó rẹ̀, Jèhófà sì ṣíjú àánú wò ó.*+ 20 Láàárín ọdún kan,* Hánà lóyún, ó bí ọmọkùnrin kan, ó sì pe orúkọ+ rẹ̀ ní Sámúẹ́lì,* torí ó sọ pé, “ọwọ́ Jèhófà ni mo ti béèrè rẹ̀.”
21 Nígbà tó yá, Ẹlikénà àti gbogbo agbo ilé rẹ̀ lọ láti rú ẹbọ ọdọọdún sí Jèhófà,+ kí ó sì mú ọrẹ tí ó jẹ́jẹ̀ẹ́ wá. 22 Àmọ́ Hánà kò lọ,+ torí ó sọ fún ọkọ rẹ̀ pé: “Gbàrà tí mo bá ti gba ọmú lẹ́nu ọmọdékùnrin náà, màá mú un wá, á fara hàn níwájú Jèhófà, á sì máa gbé ibẹ̀ láti ìgbà náà lọ.”+ 23 Ẹlikénà ọkọ rẹ̀ sọ fún un pé: “Ohun tí o bá mọ̀ pé ó dára jù* ni kí o ṣe. Dúró sí ilé títí wàá fi gba ọmú lẹ́nu rẹ̀. Kí Jèhófà jẹ́ kó rí bí o ṣe sọ.” Torí náà, obìnrin náà dúró sí ilé, ó sì ń tọ́jú ọmọ rẹ̀ títí ó fi gba ọmú lẹ́nu rẹ̀.
24 Gbàrà tó gba ọmú lẹ́nu ọmọ náà, ó mú un lọ sí Ṣílò pẹ̀lú akọ màlúù ọlọ́dún mẹ́ta àti ìyẹ̀fun tó kún òṣùwọ̀n eéfà* kan àti ìṣà* wáìnì+ ńlá kan. Ó wá sí ilé Jèhófà ní Ṣílò,+ ó sì mú ọmọdékùnrin náà dání. 25 Wọ́n pa akọ màlúù náà, wọ́n sì mú ọmọdékùnrin náà wá sọ́dọ̀ Élì. 26 Hánà wá sọ fún Élì pé: “Jọ̀ọ́, olúwa mi! Bí o ti wà láàyè,* olúwa mi, èmi ni obìnrin tó dúró lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ ní ibí yìí láti gbàdúrà sí Jèhófà.+ 27 Ọmọdékùnrin yìí ni mo gbàdúrà nípa rẹ̀, Jèhófà sì fún mi ní ohun tí mo béèrè lọ́wọ́ rẹ̀.+ 28 Èmi náà sì wá láti fi í fún Jèhófà. Gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀ ló máa fi jẹ́ ti Jèhófà.”
Ọkùnrin náà* sì forí balẹ̀ níbẹ̀ fún Jèhófà.
2 Nígbà náà, Hánà gbàdúrà pé:
Ẹnu mi gbọ̀rọ̀ lójú àwọn ọ̀tá mi,
Nítorí àwọn iṣẹ́ ìgbàlà rẹ ń mú inú mi dùn.
3 Ẹ má ṣe máa fọ́nnu;
Ẹ má ṣe jẹ́ kí ọ̀rọ̀ ìgbéraga ti ẹnu yín jáde,
Nítorí Jèhófà jẹ́ Ọlọ́run ìmọ̀,+
Òun sì ni ó ń ṣàyẹ̀wò nǹkan lọ́nà tó tọ́.
5 Àwọn tó ń jẹ àjẹyó á fi ara wọn ṣe alágbàṣe nítorí oúnjẹ,
Àmọ́ ebi ò ní pa àwọn tí ebi ń pa mọ́.+
8 Ó ń gbé aláìní dìde látinú eruku;
Ti Jèhófà ni àwọn ìpìlẹ̀ ayé,+
Ó sì gbé ilẹ̀ tó ń mú èso jáde ka orí wọn.
9 Ó ń dáàbò bo ìṣísẹ̀ àwọn adúróṣinṣin rẹ̀,+
Ṣùgbọ́n a ó pa àwọn ẹni burúkú lẹ́nu mọ́ nínú òkùnkùn,+
Nítorí kì í ṣe nípa agbára ni èèyàn fi ń borí.+
11 Ìgbà náà ni Ẹlikénà lọ sí ilé rẹ̀ ní Rámà, àmọ́ ọmọdékùnrin náà di òjíṣẹ́* Jèhófà+ níwájú àlùfáà Élì.
12 Àwọn ọmọkùnrin Élì jẹ́ èèyàn burúkú;+ wọn ò ka Jèhófà sí. 13 Ohun tí wọ́n ń ṣe sí ìpín tó tọ́ sí àwọn àlùfáà látọ̀dọ̀ àwọn èèyàn nìyí:+ Nígbàkigbà tí ọkùnrin èyíkéyìí bá ń rú ẹbọ, ìránṣẹ́ àlùfáà máa wá pẹ̀lú àmúga oníga mẹ́ta lọ́wọ́ rẹ̀, nígbà tí ẹran náà ṣì ń hó lórí iná, 14 á sì tì í bọ inú agbada tàbí ìkòkò oníga méjì tàbí ìkòkò irin tàbí ìkòkò oníga kan. Ohunkóhun tí àmúga náà bá mú wá sókè ni àlùfáà yóò mú. Bí wọ́n ṣe ń ṣe nìyẹn ní Ṣílò sí gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó ń wá síbẹ̀. 15 Bákan náà, kí ọkùnrin tó ń rú ẹbọ tó mú ọ̀rá rú èéfín rárá,+ ìránṣẹ́ àlùfáà máa wá, á sì sọ fún un pé: “Fún àlùfáà ní ẹran tó máa yan. Kò ní gba ẹran bíbọ̀ lọ́wọ́ rẹ, àfi ẹran tútù.” 16 Nígbà tí ọkùnrin náà bá sọ fún un pé: “Jẹ́ kí wọ́n kọ́kọ́ mú ọ̀rá rú èéfín ná,+ lẹ́yìn ìyẹn, kí o mú ohun tí ọkàn rẹ bá fẹ́.”* Àmọ́ á sọ pé: “Rárá, fún mi báyìí-báyìí; àìjẹ́ bẹ́ẹ̀, màá mú un tipátipá!” 17 Nípa bẹ́ẹ̀, ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ìránṣẹ́ náà wá pọ̀ gan-an níwájú Jèhófà,+ nítorí àwọn ọkùnrin náà hùwà àìlọ́wọ̀ sí ọrẹ Jèhófà.
18 Sámúẹ́lì sì ń ṣe ìránṣẹ́+ níwájú Jèhófà, ó wọ* éfódì tí a fi aṣọ ọ̀gbọ̀*+ ṣe, bó tiẹ̀ jẹ́ pé ọmọdékùnrin ni. 19 Bákan náà, ìyá rẹ̀ máa ń dá aṣọ àwọ̀lékè kékeré tí kò lápá fún un, a sì mú un wá fún un lọ́dọọdún nígbà tí òun àti ọkọ rẹ̀ bá wá láti rú ẹbọ ọdọọdún.+ 20 Élì súre fún Ẹlikénà àti ìyàwó rẹ̀, ó sọ pé: “Kí Jèhófà fún ọ ní ọmọ láti ọ̀dọ̀ ìyàwó yìí kí ó lè dípò èyí tí ẹ fún Jèhófà.”+ Wọ́n sì pa dà lọ sílé. 21 Jèhófà ṣíjú àánú wo Hánà, ó wá lóyún,+ ó sì bí ọmọkùnrin mẹ́ta sí i àti ọmọbìnrin méjì. Ọmọdékùnrin náà Sámúẹ́lì sì ń dàgbà níwájú Jèhófà.+
22 Élì ti darúgbó gan-an, àmọ́ ó ti gbọ́ gbogbo ohun tí àwọn ọmọ rẹ̀ ń ṣe+ sí gbogbo Ísírẹ́lì àti bí wọ́n ṣe ń bá àwọn obìnrin tó ń sìn ní ẹnu ọ̀nà àgọ́ ìpàdé sùn.+ 23 Ó sì máa ń sọ fún wọn pé: “Kí ló dé tí ẹ̀ ń ṣe gbogbo nǹkan yìí? Ohun tí mò ń gbọ́ nípa yín látọ̀dọ̀ gbogbo èèyàn kò dáa. 24 Kò dáa bẹ́ẹ̀, ẹ̀yin ọmọ mi, ìròyìn tí mò ń gbọ́ tí wọ́n ń sọ láàárín àwọn èèyàn Jèhófà kò dáa. 25 Bí èèyàn bá ṣẹ èèyàn bíi tirẹ̀, ẹnì kan lè bá a bẹ Jèhófà;* àmọ́ tó bá jẹ́ pé Jèhófà ni èèyàn ṣẹ̀,+ ta ló máa gbàdúrà fún un?” Ṣùgbọ́n wọn kò fetí sí bàbá wọn, nítorí pé Jèhófà ti pinnu láti pa wọ́n.+ 26 Ní gbogbo àkókò yìí, ọmọdékùnrin náà Sámúẹ́lì ń dàgbà sí i, ó sì túbọ̀ ń rí ojú rere Jèhófà àti ti àwọn èèyàn.+
27 Èèyàn Ọlọ́run kan wá sọ́dọ̀ Élì, ó sì sọ fún un pé: “Ohun tí Jèhófà sọ nìyí: ‘Ǹjẹ́ mi ò fara han ilé baba rẹ nígbà tí wọ́n wà ní Íjíbítì, tí wọ́n jẹ́ ẹrú ní ilé Fáráò?+ 28 Mo sì yàn án nínú gbogbo ẹ̀yà Ísírẹ́lì+ láti ṣe àlùfáà fún mi, kó máa gòkè lọ sórí pẹpẹ mi+ láti rú ẹbọ, kó máa sun tùràrí,* kó sì máa wọ éfódì níwájú mi. Mo sì fún ilé baba ńlá rẹ ní gbogbo àwọn ẹbọ tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì* fi iná sun.+ 29 Kí ló dé tí ẹ kò ka ẹbọ mi sí* àti ọrẹ mi tí mo pa láṣẹ ní ibùgbé mi?+ Kí ló dé tí ò ń bọlá fún àwọn ọmọkùnrin rẹ jù mí lọ, tí ẹ̀ ń fi apá tó dára jù lọ lára gbogbo ọrẹ àwọn èèyàn mi Ísírẹ́lì bọ́ ara yín sanra?+
30 “‘Ìdí nìyẹn tí Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì fi sọ pé: “Lóòótọ́, mo sọ pé ilé rẹ àti ilé baba ńlá rẹ yóò máa sìn níwájú mi nígbà gbogbo.”+ Ṣùgbọ́n ní báyìí, Jèhófà sọ pé: “Kò ní rí bẹ́ẹ̀ mọ́, nítorí pé àwọn tó ń bọlá fún mi ni màá bọlá fún,+ àmọ́ màá kórìíra àwọn tí kò kà mí sí.” 31 Wò ó! Ọjọ́ ń bọ̀ tí màá gba agbára rẹ* àti ti ilé baba rẹ, tí ẹnì kankan nínú ilé rẹ kò fi ní dàgbà.+ 32 Bí mo ti ń ṣe rere fún Ísírẹ́lì, alátakò ni wàá máa rí nínú ibùgbé mi,+ kò tún ní sí ẹni tó máa dàgbà nínú ilé rẹ mọ́ láé. 33 Èèyàn rẹ tí mi ò mú kúrò lẹ́nu sísìn níbi pẹpẹ mi yóò mú kí ojú rẹ di bàìbàì, yóò sì kó ẹ̀dùn ọkàn bá ọ,* idà àwọn èèyàn ló máa pa èyí tó pọ̀ jù lára àwọn ará ilé rẹ.+ 34 Ohun tó máa ṣẹlẹ̀ sí àwọn ọmọkùnrin rẹ méjèèjì, Hófínì àti Fíníhásì yóò jẹ́ àmì fún ọ: Ọjọ́ kan náà ni àwọn méjèèjì máa kú.+ 35 Nígbà náà, màá yan àlùfáà olóòótọ́ kan fún ara mi.+ Ohun tí ọkàn mi bá fẹ́ ni á sì máa ṣe; màá kọ́ ilé kan tó máa wà pẹ́ títí fún un, á sì máa sìn níwájú ẹni àmì òróró mi nígbà gbogbo. 36 Ẹnikẹ́ni tó bá ṣẹ́ kù nínú ilé rẹ yóò wá, yóò sì tẹrí ba fún un, yóò bẹ̀ ẹ́ pé kó fún òun ní iṣẹ́, kó lè rí owó díẹ̀ àti ìṣù búrẹ́dì, yóò sì sọ pé: “Jọ̀ọ́, fi mí sí ìdí ọ̀kan nínú iṣẹ́ àwọn àlùfáà, kí n lè máa rí búrẹ́dì jẹ.”’”+
3 Ní gbogbo àkókò yìí, ọmọdékùnrin náà Sámúẹ́lì ń ṣe ìránṣẹ́+ fún Jèhófà níwájú Élì, àmọ́ ọ̀rọ̀ látọ̀dọ̀ Jèhófà ṣọ̀wọ́n lásìkò yẹn; ìran+ rírí kò sì wọ́pọ̀.
2 Lọ́jọ́ kan, Élì ń sùn nínú yàrá rẹ̀, ojú rẹ̀ ti di bàìbàì; kò sì lè rí nǹkan kan.+ 3 Wọn kò tíì pa fìtílà Ọlọ́run,+ Sámúẹ́lì sì ń sùn nínú tẹ́ńpìlì*+ Jèhófà, níbi tí Àpótí Ọlọ́run wà. 4 Jèhófà pe Sámúẹ́lì. Ó sì dáhùn pé: “Èmi nìyí.” 5 Ó sáré lọ sọ́dọ̀ Élì, ó sì sọ pé: “Èmi nìyí, torí o pè mí.” Àmọ́ ó sọ pé: “Mi ò pè ọ́. Pa dà lọ sùn.” Torí náà, ó lọ sùn. 6 Jèhófà pè é lẹ́ẹ̀kan sí i pé: “Sámúẹ́lì!” Torí náà, Sámúẹ́lì dìde, ó sì lọ sọ́dọ̀ Élì, ó sọ pé: “Èmi nìyí, torí o pè mí.” Àmọ́ ó sọ pé: “Mi ò pè ọ́, ọmọ mi. Pa dà lọ sùn.” 7 (Sámúẹ́lì kò tíì mọ Jèhófà dáadáa, nítorí Jèhófà kò tíì bẹ̀rẹ̀ sí í bá a sọ̀rọ̀.)+ 8 Nítorí náà, Jèhófà tún pè é ní ìgbà kẹta pé: “Sámúẹ́lì!” Ó tún dìde, ó lọ sọ́dọ̀ Élì, ó sì sọ̀ pé: “Èmi nìyí, torí o pè mí.”
Élì wá mọ̀ pé Jèhófà ló ń pe ọmọdékùnrin náà. 9 Nítorí náà, Élì sọ fún Sámúẹ́lì pé: “Lọ sùn, bí ó bá tún pè ọ́, kí o sọ pé, ‘Sọ̀rọ̀, Jèhófà, nítorí ìránṣẹ́ rẹ ń gbọ́.’” Torí náà, Sámúẹ́lì lọ, ó sì sùn sí àyè rẹ̀.
10 Jèhófà wá, ó dúró níbẹ̀, ó sì pè é bíi ti àtẹ̀yìnwá pé: “Sámúẹ́lì, Sámúẹ́lì!” Sámúẹ́lì bá sọ pé: “Sọ̀rọ̀, nítorí ìránṣẹ́ rẹ ń gbọ́.” 11 Jèhófà sọ fún Sámúẹ́lì pé: “Wò ó! Màá ṣe ohun kan ní Ísírẹ́lì tó jẹ́ pé ẹnikẹ́ni tó bá gbọ́ nípa rẹ̀, etí rẹ̀ méjèèjì á hó yee.+ 12 Ní ọjọ́ yẹn, màá ṣe gbogbo ohun tí mo sọ nípa Élì àti nípa ilé rẹ̀, láti ìbẹ̀rẹ̀ dé òpin.+ 13 Sọ fún un pé màá ṣe ìdájọ́ tó máa wà títí láé fún ilé rẹ̀ nítorí ẹ̀ṣẹ̀ tí ó mọ̀ nípa rẹ̀,+ torí àwọn ọmọ rẹ̀ ń sọ̀rọ̀ òdì sí Ọlọ́run,+ àmọ́ kò bá wọn wí.+ 14 Ìdí nìyẹn tí mo fi búra fún ilé Élì pé ẹbọ tàbí ọrẹ kò ní lè pẹ̀tù sí ẹ̀ṣẹ̀ ilé Élì láé.”+
15 Sámúẹ́lì sùn títí di àárọ̀, lẹ́yìn náà ó ṣí àwọn ilẹ̀kùn ilé Jèhófà. Ẹ̀rù ń ba Sámúẹ́lì láti sọ ìran náà fún Élì. 16 Ṣùgbọ́n Élì pe Sámúẹ́lì, ó ní: “Sámúẹ́lì, ọmọ mi!” Ó dáhùn pé: “Èmi nìyí.” 17 Ó bi í pé: “Ọ̀rọ̀ wo ló sọ fún ọ? Jọ̀wọ́, má fi pa mọ́ fún mi. Kí Ọlọ́run fi ìyà jẹ ọ́ gan-an, tí o bá fi ọ̀rọ̀ kan pa mọ́ fún mi nínú gbogbo ohun tó sọ fún ọ.” 18 Torí náà, Sámúẹ́lì sọ gbogbo ọ̀rọ̀ náà fún un, kò sì fi ohunkóhun pa mọ́ fún un. Élì sọ pé: “Jèhófà ni. Kí ó ṣe ohun tó dára ní ojú rẹ̀.”
19 Sámúẹ́lì ń dàgbà sí i, Jèhófà fúnra rẹ̀ wà pẹ̀lú rẹ̀,+ kò sì jẹ́ kí èyíkéyìí nínú gbogbo ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ láìṣẹ.* 20 Gbogbo Ísírẹ́lì láti Dánì títí dé Bíá-ṣébà sì wá mọ̀ pé Sámúẹ́lì ti di wòlíì Jèhófà. 21 Jèhófà sì ń fara hàn ní Ṣílò, nítorí Jèhófà ti jẹ́ kí Sámúẹ́lì mọ òun ní Ṣílò nípasẹ̀ ọ̀rọ̀ Jèhófà.+
4 Sámúẹ́lì bá gbogbo Ísírẹ́lì sọ̀rọ̀.
Lẹ́yìn náà, Ísírẹ́lì jáde lọ pàdé àwọn Filísínì láti bá wọn jà; wọ́n pàgọ́ sí ẹ̀gbẹ́ Ẹbinísà, àwọn Filísínì sì pàgọ́ sí Áfékì. 2 Àwọn Filísínì tò lọ́wọ̀ọ̀wọ́ láti bá Ísírẹ́lì jà, àmọ́ ìjà náà yíwọ́, àwọn Filísínì ṣẹ́gun Ísírẹ́lì, wọ́n pa nǹkan bí ẹgbẹ̀rún mẹ́rin (4,000) ọkùnrin lójú ogun ní pápá. 3 Nígbà tí àwọn èèyàn náà pa dà sí ibùdó, àwọn àgbààgbà Ísírẹ́lì sọ pé: “Kí ló dé tí Jèhófà fi jẹ́ kí àwọn Filísínì ṣẹ́gun wa lónìí?*+ Ẹ jẹ́ kí a lọ gbé àpótí májẹ̀mú Jèhófà láti Ṣílò,+ kí ó lè wà lọ́dọ̀ wa, kí ó sì gbà wá lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá wa.” 4 Nítorí náà, wọ́n rán àwọn èèyàn lọ sí Ṣílò, láti ibẹ̀, wọ́n gbé àpótí májẹ̀mú Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun, ẹni tó ń jókòó lórí* àwọn kérúbù.+ Àwọn ọmọkùnrin Élì méjèèjì, Hófínì àti Fíníhásì+ sì wà níbẹ̀ pẹ̀lú àpótí májẹ̀mú Ọlọ́run tòótọ́.
5 Gbàrà tí àpótí májẹ̀mú Jèhófà dé sí ibùdó, gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì hó yèè, tí ilẹ̀ fi mì tìtì. 6 Nígbà tí àwọn Filísínì gbọ́ ìró wọn, wọ́n sọ pé: “Kí ló fa irú ariwo yìí ní ibùdó àwọn Hébérù?” Níkẹyìn, wọ́n wá mọ̀ pé Àpótí Jèhófà ti dé sí ibùdó. 7 Ẹ̀rù ba àwọn Filísínì gan-an, wọ́n sọ pé: “Ọlọ́run ti dé sí ibùdó!”+ Ni wọ́n bá sọ pé: “A ti dáràn, nítorí irú èyí ò ṣẹlẹ̀ rí! 8 A ti dáràn! Ta ló máa gbà wá lọ́wọ́ Ọlọ́run títóbi yìí? Ọlọ́run yìí ló pa àwọn ará Íjíbítì lóríṣiríṣi ọ̀nà ní aginjù.+ 9 Ẹ jẹ́ onígboyà, kí ẹ sì ṣe bí ọkùnrin, ẹ̀yin Filísínì, kí ẹ má bàa sin àwọn Hébérù bí wọ́n ṣe sìn yín.+ Ẹ ṣe bí ọkùnrin, kí ẹ sì jà!” 10 Torí náà, àwọn Filísínì jà, wọ́n ṣẹ́gun Ísírẹ́lì,+ kálukú wọn sì sá lọ sí ilé rẹ̀. Ìpakúpa náà pọ̀; ọ̀kẹ́ kan ààbọ̀ (30,000) àwọn ọmọ ogun tó ń fẹsẹ̀ rìn ló kú lára àwọn ọmọ Ísírẹ́lì. 11 Yàtọ̀ síyẹn, wọ́n gba Àpótí Ọlọ́run, àwọn ọmọ Élì méjèèjì, Hófínì àti Fíníhásì sì kú.+
12 Lọ́jọ́ yẹn, ọkùnrin ará Bẹ́ńjámínì kan sá wá sí Ṣílò láti ojú ogun, aṣọ rẹ̀ ti ya, iyẹ̀pẹ̀ sì wà lórí rẹ̀.+ 13 Nígbà tí ọkùnrin náà dé, Élì wà lórí ìjókòó lẹ́gbẹ̀ẹ́ ọ̀nà tó ń ṣọ́nà, ọkàn rẹ̀ ò balẹ̀ nítorí Àpótí Ọlọ́run tòótọ́.+ Ọkùnrin náà lọ sínú ìlú láti ròyìn ohun tó ṣẹlẹ̀, gbogbo ìlú náà sì bẹ̀rẹ̀ sí í sunkún. 14 Nígbà tí Élì gbọ́ igbe ẹkún náà, ó béèrè pé: “Kí ló fa irú ariwo tí mò ń gbọ́ yìí?” Ní kíá, ọkùnrin náà wọlé, ó sì ròyìn ohun tó ṣẹlẹ̀ fún Élì. 15 (Ní àkókò yẹn, Élì jẹ́ ẹni ọdún méjìdínlọ́gọ́rùn-ún [98], ojú rẹ̀ là sílẹ̀, àmọ́ kò rí nǹkan kan.)+ 16 Ọkùnrin náà wá sọ fún Élì pé: “Ojú ogun ni mo ti ń bọ̀! Òní yìí gan-an ni mo sá kúrò lójú ogun.” Ni Élì bá bi í pé: “Kí ló ṣẹlẹ̀, ọmọ mi?” 17 Ọkùnrin tó mú ìròyìn náà wá sì sọ pé: “Ísírẹ́lì ti sá níwájú àwọn Filísínì, wọ́n sì ti ṣẹ́gun àwọn èèyàn wa lọ́nà tó kàmàmà+ àti pé àwọn ọmọ rẹ méjèèjì, Hófínì àti Fíníhásì ti kú,+ wọ́n sì ti gba Àpótí Ọlọ́run tòótọ́.”+
18 Ní gbàrà tó mẹ́nu kan Àpótí Ọlọ́run tòótọ́, Élì ṣubú sẹ́yìn láti orí ìjókòó tó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ ẹnubodè, ọrùn rẹ̀ ṣẹ́, ó sì kú, nítorí pé ó ti darúgbó, ó sì sanra. Ogójì (40) ọdún ló fi ṣèdájọ́ Ísírẹ́lì. 19 Aya ọmọ rẹ̀, ìyẹn ìyàwó Fíníhásì wà nínú oyún, kò sì ní pẹ́ bímọ. Nígbà tó gbọ́ ìròyìn pé wọ́n ti gba Àpótí Ọlọ́run tòótọ́ àti pé bàbá ọkọ rẹ̀ àti ọkọ rẹ̀ ti kú, ó tẹ̀ ba, lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ ó bẹ̀rẹ̀ sí í rọbí, ó sì bímọ. 20 Bí ó ṣe ń kú lọ, àwọn obìnrin tó dúró tì í sọ pé: “Má bẹ̀rù, nítorí ọkùnrin lo bí.” Kò dáhùn, kò sì fiyè sí i.* 21 Ṣùgbọ́n ó pe ọmọ náà ní Íkábódì,*+ ó ní: “Ògo ti kúrò ní Ísírẹ́lì lọ sí ìgbèkùn,”+ ó ń tọ́ka sí bí wọ́n ṣe gba Àpótí Ọlọ́run tòótọ́ àti ohun tó ṣẹlẹ̀ sí bàbá ọkọ rẹ̀ àti ọkọ rẹ̀.+ 22 Ó sọ pé: “Ògo ti kúrò ní Ísírẹ́lì lọ sí ìgbèkùn, nítorí wọ́n ti gba Àpótí Ọlọ́run tòótọ́.”+
5 Nígbà tí àwọn Filísínì gba Àpótí+ Ọlọ́run tòótọ́, wọ́n gbé e láti Ẹbinísà wá sí Áṣídódì. 2 Àwọn Filísínì gbé Àpótí Ọlọ́run tòótọ́ wá sínú ilé* Dágónì, wọ́n sì gbé e sẹ́gbẹ̀ẹ́ Dágónì.+ 3 Nígbà tí àwọn ará Áṣídódì dìde ní kùtùkùtù ọjọ́ kejì, Dágónì ti ṣubú, ó sì dojú bolẹ̀ níwájú Àpótí Jèhófà.+ Torí náà, wọ́n gbé Dágónì, wọ́n sì dá a pa dà sí àyè rẹ̀.+ 4 Nígbà tí wọ́n dìde ní àárọ̀ kùtù ọjọ́ tó tẹ̀ lé e, Dágónì tún ti ṣubú, ó sì dojú bolẹ̀ níwájú Àpótí Jèhófà. Orí Dágónì àti àtẹ́lẹwọ́ rẹ̀ méjèèjì tí gé kúrò, wọ́n sì wà ní ibi àbáwọlé. Ibi tó dà bí ẹja lára rẹ̀ nìkan* ló ṣẹ́ kù. 5 Ìdí nìyẹn tí àwọn àlùfáà Dágónì àti gbogbo àwọn tó ń wọnú ilé Dágónì kì í fi í tẹ ibi àbáwọlé Dágónì ní Áṣídódì títí di òní yìí.
6 Ọwọ́ Jèhófà le mọ́ àwọn ará Áṣídódì, ó kó ìyọnu bá wọn, ó sì ń fi jẹ̀díjẹ̀dí* kọ lu Áṣídódì àti àwọn ìpínlẹ̀ rẹ̀.+ 7 Nígbà tí àwọn èèyàn Áṣídódì rí ohun tó ń ṣẹlẹ̀, wọ́n sọ pé: “Ẹ má ṣe jẹ́ kí Àpótí Ọlọ́run Ísírẹ́lì máa gbé pẹ̀lú wa, nítorí pé ọwọ́ rẹ̀ ti le mọ́ àwa àti Dágónì ọlọ́run wa.” 8 Nítorí náà, wọ́n ránṣẹ́ pe gbogbo àwọn alákòóso Filísínì jọ, wọ́n bi wọ́n pé: “Kí ni ká ṣe sí Àpótí Ọlọ́run Ísírẹ́lì?” Wọ́n fèsì pé: “Ẹ jẹ́ kí a gbé Àpótí Ọlọ́run Ísírẹ́lì lọ sí Gátì.”+ Torí náà, wọ́n gbé Àpótí Ọlọ́run Ísírẹ́lì lọ síbẹ̀.
9 Lẹ́yìn tí wọ́n gbé e dé ibẹ̀, ọwọ́ Jèhófà wá sórí ìlú náà, ó sì kó jìnnìjìnnì bá wọn. Ó fìyà jẹ àwọn èèyàn ìlú náà látorí ẹni kékeré dórí ẹni ńlá, jẹ̀díjẹ̀dí sì kọ lù wọ́n.+ 10 Nítorí náà, wọ́n gbé Àpótí Ọlọ́run tòótọ́ ránṣẹ́ sí Ẹ́kírónì,+ àmọ́ gbàrà tí Àpótí Ọlọ́run tòótọ́ dé Ẹ́kírónì, àwọn ará Ẹ́kírónì bẹ̀rẹ̀ sí í kígbe pé: “Yéè, wọ́n ti gbé Àpótí Ọlọ́run Ísírẹ́lì wá sọ́dọ̀ wa láti pa àwa àti àwọn èèyàn wa!”+ 11 Nítorí náà, wọ́n ránṣẹ́ pe gbogbo àwọn alákòóso Filísínì jọ, wọ́n sì sọ pé: “Ẹ gbé Àpótí Ọlọ́run Ísírẹ́lì kúrò lọ́dọ̀ wa, ẹ dá a pa dà sí àyè rẹ̀, kó má bàa pa àwa àti àwọn èèyàn wa.” Nítorí ìbẹ̀rù ikú ti gba gbogbo ìlú náà kan; ọwọ́ Ọlọ́run tòótọ́ sì ti le mọ́ àwọn èèyàn ibẹ̀,+ 12 jẹ̀díjẹ̀dí ti kọ lu àwọn tí kò tíì kú. Igbe ìlú náà fún ìrànlọ́wọ́ sì ti dé ọ̀run.
6 Oṣù méje ni Àpótí+ Jèhófà fi wà ní ìpínlẹ̀ àwọn Filísínì. 2 Àwọn Filísínì pe àwọn àlùfáà àti àwọn woṣẹ́woṣẹ́,+ wọ́n béèrè pé: “Kí ni ká ṣe sí Àpótí Jèhófà? Ẹ jẹ́ ká mọ bí a ṣe máa dá a pa dà sí àyè rẹ̀.” 3 Wọ́n fèsì pé: “Bí ẹ bá máa dá àpótí májẹ̀mú Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì pa dà, ẹ má ṣe dá a pa dà láìsí ọrẹ. Ẹ gbọ́dọ̀ dá a pa dà pẹ̀lú ọrẹ ẹ̀bi.+ Ìgbà yẹn ni ara yín máa tó yá, tí ẹ sì máa mọ ìdí tí ọwọ́ rẹ̀ ṣì fi le mọ́ yín.” 4 Ni wọ́n bá béèrè pé: “Ọrẹ ẹ̀bi wo ni ká fi ránṣẹ́ sí i?” Wọ́n sọ pé: “Ẹ fi jẹ̀díjẹ̀dí* wúrà márùn-ún àti eku wúrà márùn-ún ránṣẹ́, gẹ́gẹ́ bí iye àwọn alákòóso Filísínì,+ nítorí irú àjàkálẹ̀ àrùn kan náà ni ó kọ lu ẹnì kọ̀ọ̀kan yín àti àwọn alákòóso yín. 5 Ẹ ṣe àwọn ère jẹ̀díjẹ̀dí yín àti àwọn ère eku yín+ tó ń pa ilẹ̀ náà run, kí ẹ sì bọlá fún Ọlọ́run Ísírẹ́lì. Bóyá ó lè dẹ ọwọ́ rẹ̀ lára yín, lára ọlọ́run yín àti ilẹ̀ yín.+ 6 Kí nìdí tí ẹ ó fi mú kí ọkàn yín le bí Íjíbítì àti Fáráò ṣe mú kí ọkàn wọn le?+ Nígbà tí Ọlọ́run fìyà jẹ wọ́n,+ ńṣe ni wọ́n jẹ́ kí Ísírẹ́lì máa lọ, wọ́n sì lọ.+ 7 Ní báyìí, ẹ ṣètò kẹ̀kẹ́ tuntun kan àti abo màlúù méjì tó ní ọmọ, tí a kò ti àjàgà bọ̀ lọ́rùn rí. Kí ẹ wá so àwọn abo màlúù náà mọ́ kẹ̀kẹ́ náà, àmọ́ kí ẹ kó àwọn ọmọ màlúù náà kúrò lọ́dọ̀ wọn pa dà sílé. 8 Ẹ gbé Àpótí Jèhófà sórí kẹ̀kẹ́ náà, kí ẹ sì kó àwọn ère wúrà tí ẹ fẹ́ fi ránṣẹ́ sí i gẹ́gẹ́ bí ọrẹ ẹ̀bi sínú àpótí tó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀.+ Kí ẹ wá rán an lọ, 9 kí ẹ sì máa wò ó: Tó bá jẹ́ pé ọ̀nà Bẹti-ṣémẹ́ṣì+ ló lọ, ní ìpínlẹ̀ rẹ̀, á jẹ́ pé Ọlọ́run wọn ló fa ibi ńlá tó bá wa yìí. Àmọ́ tí kò bá rí bẹ́ẹ̀, a ó mọ̀ pé kì í ṣe ọwọ́ rẹ̀ ló kọ lù wá; ó kàn ṣèèṣì wáyé bẹ́ẹ̀ ni.”
10 Àwọn ọkùnrin náà ṣe bẹ́ẹ̀ gẹ́lẹ́. Wọ́n mú abo màlúù méjì tó ní ọmọ, wọ́n sì so wọ́n mọ́ kẹ̀kẹ́ náà, wọ́n kó àwọn ọmọ wọn sínú ọgbà ẹran nílé. 11 Lẹ́yìn náà, wọ́n gbé Àpótí Jèhófà sórí kẹ̀kẹ́ náà àti àpótí tí àwọn eku wúrà àti àwọn ère jẹ̀díjẹ̀dí wọn wà nínú rẹ̀. 12 Àwọn abo màlúù náà lọ tààràtà sí ọ̀nà Bẹti-ṣémẹ́ṣì.+ Ojú ọ̀nà ni wọ́n ń gbà lọ, tí wọ́n ń ké mùúù bí wọ́n ṣe ń lọ; wọn ò yà sí ọ̀tún tàbí sí òsì. Ní gbogbo àkókò yẹn, àwọn alákòóso Filísínì ń rìn tẹ̀ lé wọn títí dé ààlà Bẹti-ṣémẹ́ṣì. 13 Àwọn èèyàn Bẹti-ṣémẹ́ṣì ń kórè àlìkámà* ní àfonífojì.* Nígbà tí wọ́n gbójú sókè, tí wọ́n rí Àpótí náà, inú wọn dùn gan-an bí wọ́n ṣe rí i. 14 Kẹ̀kẹ́ náà wọnú pápá Jóṣúà ará Bẹti-ṣémẹ́ṣì, ó sì dúró síbẹ̀ lẹ́gbẹ̀ẹ́ òkúta ńlá kan. Wọ́n wá la igi kẹ̀kẹ́ náà sí wẹ́wẹ́, wọ́n sì fi àwọn abo màlúù+ náà rú ẹbọ sísun sí Jèhófà.
15 Àwọn ọmọ Léfì+ sọ Àpótí Jèhófà kalẹ̀ àti àpótí tó wà pẹ̀lú rẹ̀, èyí tí àwọn ohun tí wọ́n fi wúrà ṣe wà nínú rẹ̀, wọ́n sì gbé wọn sórí òkúta ńlá náà. Àwọn ọkùnrin Bẹti-ṣémẹ́ṣì+ rú àwọn ẹbọ sísun, wọ́n sì tún rú àwọn ẹbọ sí Jèhófà ní ọjọ́ yẹn.
16 Nígbà tí àwọn alákòóso Filísínì márààrún rí i, wọ́n pa dà sí Ẹ́kírónì ní ọjọ́ yẹn. 17 Àwọn jẹ̀díjẹ̀dí wúrà tí àwọn Filísínì fi ránṣẹ́ láti fi ṣe ọrẹ ẹ̀bi fún Jèhófà nìyí:+ ọ̀kan fún Áṣídódì,+ ọ̀kan fún Gásà, ọ̀kan fún Áṣíkẹ́lónì, ọ̀kan fún Gátì,+ ọ̀kan fún Ẹ́kírónì.+ 18 Iye àwọn eku wúrà náà jẹ́ iye gbogbo àwọn ìlú Filísínì tí wọ́n jẹ́ ti àwọn alákòóso márààrún, ìyẹn àwọn ìlú olódi àti àwọn abúlé tó wà ní ìgbèríko.
Òkúta ńlá tí wọ́n gbé Àpótí Jèhófà lé sì jẹ́ ẹ̀rí títí di òní yìí ní pápá Jóṣúà ará Bẹti-ṣémẹ́ṣì. 19 Àmọ́ Ọlọ́run pa àwọn ọkùnrin Bẹti-ṣémẹ́ṣì, torí pé wọ́n wo Àpótí Jèhófà. Ó pa ẹgbẹ̀rún lọ́nà àádọ́ta ó lé àádọ́rin (50,070)* lára àwọn èèyàn náà, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í ṣọ̀fọ̀ nítorí pé Jèhófà ti pa wọ́n lọ rẹpẹtẹ.+ 20 Torí náà, àwọn èèyàn Bẹti-ṣémẹ́ṣì béèrè pé: “Ta ló lè dúró níwájú Jèhófà Ọlọ́run mímọ́ yìí,+ ọ̀dọ̀ ta ló sì máa lọ tí á fi kúrò lọ́dọ̀ wa?”+ 21 Ìgbà náà ni wọ́n rán àwọn òjíṣẹ́ sí àwọn tó ń gbé ní Kiriati-jéárímù+ pé: “Àwọn Filísínì ti dá Àpótí Jèhófà pa dà o. Ẹ wá gbé e lọ sọ́dọ̀ yín.”+
7 Nítorí náà, àwọn ọkùnrin Kiriati-jéárímù wá, wọ́n gbé Àpótí Jèhófà lọ sí ilé Ábínádábù+ tó wà lórí òkè, wọ́n sì ya Élíásárì ọmọ rẹ̀ sí mímọ́ láti máa ṣọ́ Àpótí Jèhófà.
2 Odindi ogún (20) ọdún kọjá lẹ́yìn tí Àpótí náà ti dé Kiriati-jéárímù kí gbogbo ilé Ísírẹ́lì tó bẹ̀rẹ̀ sí í wá* Jèhófà.+ 3 Sámúẹ́lì sì sọ fún gbogbo ilé Ísírẹ́lì pé: “Bí ẹ bá máa fi gbogbo ọkàn yín pa dà sọ́dọ̀ Jèhófà,+ ẹ mú àwọn ọlọ́run àjèjì+ àti àwọn ère Áṣítórétì+ kúrò láàárín yín, kí ẹ sì darí ọkàn yín tààrà sọ́dọ̀ Jèhófà, kí ẹ máa sin òun nìkan ṣoṣo,+ yóò sì gbà yín lọ́wọ́ àwọn Filísínì.”+ 4 Ni àwọn ọmọ Ísírẹ́lì bá mú àwọn Báálì àti àwọn ère Áṣítórétì kúrò, wọ́n sì ń sin Jèhófà nìkan ṣoṣo.+
5 Sámúẹ́lì wá sọ pé: “Ẹ kó gbogbo Ísírẹ́lì jọ sí Mísípà,+ màá sì gbàdúrà sí Jèhófà nítorí yín.”+ 6 Torí náà, wọ́n kóra jọ sí Mísípà, wọ́n pọn omi, wọ́n dà á jáde níwájú Jèhófà, wọ́n sì gba ààwẹ̀ ní ọjọ́ yẹn.+ Ibẹ̀ ni wọ́n ti sọ pé: “A ti dẹ́ṣẹ̀ sí Jèhófà.”+ Sámúẹ́lì sì bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe onídàájọ́+ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní Mísípà.
7 Nígbà tí àwọn Filísínì gbọ́ pé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ti kóra jọ sí Mísípà, àwọn alákòóso Filísínì+ lọ dojú kọ Ísírẹ́lì. Bí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe gbọ́ báyìí, ẹ̀rù bà wọ́n nítorí àwọn Filísínì. 8 Nítorí náà, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sọ fún Sámúẹ́lì pé: “Má ṣe dákẹ́ láti máa ké pe Jèhófà Ọlọ́run wa pé kó ràn wá lọ́wọ́,+ kó sì gbà wá lọ́wọ́ àwọn Filísínì.” 9 Sámúẹ́lì wá mú ọ̀dọ́ àgùntàn kan tó ṣì ń mu ọmú, ó sì fi rú odindi ẹbọ sísun+ sí Jèhófà; Sámúẹ́lì ké pe Jèhófà pé kó ran Ísírẹ́lì lọ́wọ́, Jèhófà sì dá a lóhùn.+ 10 Bí Sámúẹ́lì ṣe ń rú ẹbọ sísun lọ́wọ́, àwọn Filísínì gbógun dé láti bá Ísírẹ́lì jà. Jèhófà mú kí ààrá ńlá kan sán+ sórí àwọn Filísínì ní ọjọ́ yẹn, ó kó ìdààmú bá wọn,+ ó sì mú kí Ísírẹ́lì ṣẹ́gun wọn.+ 11 Ni àwọn ọkùnrin Ísírẹ́lì bá jáde kúrò ní Mísípà, wọ́n ń lépa àwọn Filísínì, wọ́n sì ń pa wọ́n títí dé gúúsù Bẹti-kárì. 12 Ìgbà náà ni Sámúẹ́lì gbé òkúta kan,+ ó sì gbé e kalẹ̀ sí àárín Mísípà àti Jẹ́ṣánà, ó pe orúkọ rẹ̀ ní Ẹbinísà* torí ó sọ pé: “Jèhófà ti ń ràn wá lọ́wọ́ títí di ìsinsìnyí.”+ 13 Bí wọ́n ṣe borí àwọn Filísínì nìyẹn, wọn ò sì pa dà wá sí ìpínlẹ̀ Ísírẹ́lì mọ́;+ ńṣe ni ọwọ́ Jèhófà ń le mọ́ àwọn Filísínì ní gbogbo ọjọ́ ayé Sámúẹ́lì.+ 14 Yàtọ̀ síyẹn, àwọn ìlú tí àwọn Filísínì ti gbà lọ́wọ́ Ísírẹ́lì ni wọ́n dá pa dà fún Ísírẹ́lì, láti Ẹ́kírónì títí dé Gátì, Ísírẹ́lì sì gba ìpínlẹ̀ wọn pa dà lọ́wọ́ àwọn Filísínì.
Àlàáfíà sì tún wà láàárín Ísírẹ́lì àti àwọn Ámórì.+
15 Sámúẹ́lì sì ń ṣe ìdájọ́ Ísírẹ́lì ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀.+ 16 Lọ́dọọdún, ó máa ń rin ìrìn àjò yí ká Bẹ́tẹ́lì,+ Gílígálì+ àti Mísípà,+ ó sì ń ṣe ìdájọ́ Ísírẹ́lì ní gbogbo ibí yìí. 17 Ṣùgbọ́n, ó máa ń pa dà sí Rámà,+ torí ibẹ̀ ni ilé rẹ̀ wà, ó tún máa ń ṣe ìdájọ́ Ísírẹ́lì níbẹ̀. Ó sì mọ pẹpẹ kan síbẹ̀ fún Jèhófà.+
8 Nígbà tí Sámúẹ́lì darúgbó, ó yan àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ láti máa ṣe onídàájọ́ Ísírẹ́lì. 2 Orúkọ ọmọkùnrin rẹ̀ àkọ́bí ni Jóẹ́lì, orúkọ èkejì sì ni Ábíjà;+ wọ́n jẹ́ onídàájọ́ ní Bíá-ṣébà. 3 Àmọ́ àwọn ọmọ rẹ̀ kò tẹ̀ lé àpẹẹrẹ rẹ̀; ọkàn wọn ń fà sí jíjẹ èrè tí kò tọ́,+ wọ́n ń gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀,+ wọ́n sì ń yí ìdájọ́ po.+
4 Nígbà tó yá, gbogbo àgbààgbà Ísírẹ́lì kóra jọ, wọ́n sì wá sọ́dọ̀ Sámúẹ́lì ní Rámà. 5 Wọ́n sọ fún un pé: “Wò ó! O ti darúgbó, ṣùgbọ́n àwọn ọmọ rẹ kò tẹ̀ lé àpẹẹrẹ rẹ. Ní báyìí, yan ọba fún wa tí á máa ṣe ìdájọ́ wa bíi ti gbogbo orílẹ̀-èdè yòókù.”+ 6 Àmọ́, kò dùn mọ́ Sámúẹ́lì nínú* bí wọ́n ṣe sọ pé: “Fún wa ní ọba tí á máa ṣe ìdájọ́ wa.” Sámúẹ́lì wá gbàdúrà sí Jèhófà, 7 Jèhófà sì sọ fún Sámúẹ́lì pé: “Fetí sí gbogbo ohun tí àwọn èèyàn náà sọ fún ọ; nítorí kì í ṣe ìwọ ni wọ́n kọ̀, èmi ni wọ́n kọ̀ ní ọba wọn.+ 8 Bí wọ́n ti ń ṣe láti ọjọ́ tí mo ti mú wọn jáde kúrò ní Íjíbítì ni wọ́n ń ṣe títí di òní yìí; wọ́n á fi mí sílẹ̀,+ wọ́n á sì lọ máa sin àwọn ọlọ́run míì,+ ohun kan náà ni wọ́n ń ṣe sí ọ báyìí. 9 Ní báyìí fetí sí wọn. Síbẹ̀, kìlọ̀ fún wọn gidigidi; sọ ohun tí ọba tó máa jẹ lé wọn lórí máa lẹ́tọ̀ọ́ láti gbà.”
10 Torí náà, Sámúẹ́lì sọ gbogbo ọ̀rọ̀ Jèhófà fún àwọn èèyàn tí wọ́n ní kí Sámúẹ́lì fún àwọn ní ọba. 11 Ó ní: “Ohun tí ọba tó bá jẹ lórí yín máa lẹ́tọ̀ọ́ láti gbà nìyí:+ Á mú àwọn ọmọkùnrin yín,+ á sì fi wọ́n sínú àwọn kẹ̀kẹ́ ẹṣin rẹ̀,+ á wá sọ wọ́n di agẹṣin rẹ̀,+ àwọn kan á sì ní láti máa sáré níwájú àwọn kẹ̀kẹ́ ẹṣin rẹ̀. 12 Á yan àwọn olórí ẹgbẹẹgbẹ̀rún+ àti àwọn olórí àràádọ́ta+ fún ara rẹ̀, àwọn kan á máa bá a túlẹ̀,+ wọ́n á máa bá a kórè,+ wọ́n á sì máa ṣe ohun ìjà fún un àti àwọn ohun èlò kẹ̀kẹ́ ẹṣin rẹ̀.+ 13 Á mú àwọn ọmọbìnrin yín, á sì sọ wọ́n di olùpo òróró ìpara,* alásè àti olùṣe búrẹ́dì.+ 14 Á gba èyí tó dára jù lára àwọn oko yín àti àwọn ọgbà àjàrà+ yín àti àwọn oko ólífì yín, á sì fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀. 15 Á gba ìdá mẹ́wàá àwọn oko ọkà yín àti àwọn ọgbà àjàrà yín, á sì fún àwọn òṣìṣẹ́ ààfin rẹ̀ àti àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀. 16 Á gba àwọn ìránṣẹ́ yín lọ́kùnrin àti lóbìnrin, àwọn ọ̀wọ́ ẹran yín tó dára jù àti àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ yín, á sì máa lò wọ́n fún iṣẹ́ tirẹ̀.+ 17 Á gba ìdá mẹ́wàá agbo ẹran yín,+ ẹ ó sì di ìránṣẹ́ rẹ̀. 18 Ọjọ́ náà ń bọ̀ tí ẹ máa ké jáde nítorí ọba tí ẹ yàn fún ara yín,+ àmọ́ Jèhófà kò ní dá yín lóhùn ní ọjọ́ yẹn.”
19 Síbẹ̀, àwọn èèyàn náà kò fetí sí ohun tí Sámúẹ́lì sọ fún wọn, wọ́n ní: “Àní sẹ́, a ti pinnu láti ní ọba tiwa. 20 A ó sì wá dà bíi gbogbo orílẹ̀-èdè yòókù, ọba wa yóò sì máa ṣe ìdájọ́ wa, yóò máa darí wa, yóò sì máa jagun fún wa.” 21 Lẹ́yìn tí Sámúẹ́lì gbọ́ gbogbo ọ̀rọ̀ tí àwọn èèyàn náà sọ, ó tún ọ̀rọ̀ náà sọ fún* Jèhófà. 22 Jèhófà sọ fún Sámúẹ́lì pé: “Fetí sí wọn, kí o sì fi ọba jẹ lé wọn lórí.”+ Sámúẹ́lì wá sọ fún àwọn ọkùnrin Ísírẹ́lì pé: “Kí kálukú yín pa dà sí ìlú rẹ̀.”
9 Ọkùnrin ará Bẹ́ńjámínì kan wà tó ń jẹ́ Kíṣì,+ ọmọ Ábíélì, ọmọ Sérórì, ọmọ Békórátì, ọmọ Áfíà, ọmọ ẹ̀yà Bẹ́ńjámínì,+ ó ní ọrọ̀ gan-an. 2 Ó ní ọmọkùnrin kan tó ń jẹ́ Sọ́ọ̀lù,+ ọ̀dọ́ ni, ó sì rẹwà, kò sí ọkùnrin kankan lára àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó rẹwà tó o; tí ó bá dúró, kò sí ẹnì kankan lára àwọn èèyàn náà tó ga dé èjìká rẹ̀.
3 Nígbà tí àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́* Kíṣì bàbá Sọ́ọ̀lù sọ nù, Kíṣì sọ fún Sọ́ọ̀lù ọmọ rẹ̀ pé: “Jọ̀wọ́, mú ọ̀kan lára àwọn ìránṣẹ́ dání, kí o sì lọ wá àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà.” 4 Ni wọ́n bá gba agbègbè olókè Éfúrémù kọjá àti ilẹ̀ Ṣálíṣà, àmọ́ wọn ò rí wọn. Wọ́n rin ìrìn àjò dé ilẹ̀ Ṣáálímù, àmọ́ àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà ò sí níbẹ̀. Gbogbo ilẹ̀ àwọn ọmọ Bẹ́ńjámínì ni wọ́n dé, síbẹ̀ wọn ò rí wọn.
5 Wọ́n dé ilẹ̀ Súfì, Sọ́ọ̀lù wá sọ fún ìránṣẹ́ rẹ̀ tó wà pẹ̀lú rẹ̀ pé: “Wá, jẹ́ ká pa dà, kí bàbá mi má bàa bẹ̀rẹ̀ sí í dààmú nípa wa dípò àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà.”+ 6 Àmọ́ ìránṣẹ́ náà fèsì pé: “Wò ó, èèyàn Ọlọ́run kan wà ní ìlú yìí, ẹni iyì sì ni ọkùnrin náà. Gbogbo ohun tó bá sọ ló dájú pé á ṣẹ.+ Jẹ́ ká lọ síbẹ̀ báyìí. Bóyá ó lè sọ ibi tí a máa wá wọn sí fún wa.” 7 Ni Sọ́ọ̀lù bá sọ fún ìránṣẹ́ rẹ̀ pé: “Tí a bá máa lọ, kí ni a máa fún ọkùnrin náà? Kò sí oúnjẹ kankan nínú àpò wa; kò sí ẹ̀bùn kankan tí a lé lọ fún èèyàn Ọlọ́run tòótọ́ náà. Kí la ní lọ́wọ́?” 8 Ìránṣẹ́ náà tún dá Sọ́ọ̀lù lóhùn pé: “Wò ó! Ìdá mẹ́rin ṣékélì* fàdákà wà lọ́wọ́ mi. Màá fún èèyàn Ọlọ́run tòótọ́ náà, yóò sì sọ ibi tí a máa wá wọn sí fún wa.” 9 (Láyé àtijọ́ ní Ísírẹ́lì, ohun tí ẹni tó bá fẹ́ wá Ọlọ́run máa sọ nìyí: “Ẹ wá, ẹ jẹ́ ká lọ sọ́dọ̀ aríran.”+ Nítorí àwọn tí wọ́n ń pè ní aríran láyé àtijọ́ ni à ń pè ní wòlíì lóde òní.) 10 Sọ́ọ̀lù wá sọ fún ìránṣẹ́ rẹ̀ pé: “Ọ̀rọ̀ rẹ dára. Jẹ́ ká lọ.” Torí náà, wọ́n lọ sí ìlú tí èèyàn Ọlọ́run tòótọ́ náà wà.
11 Bí wọ́n ṣe ń gòkè lọ sí ìlú náà, wọ́n pàdé àwọn ọmọbìnrin tí wọ́n fẹ́ lọ pọn omi. Torí náà, wọ́n béèrè lọ́wọ́ wọn pé: “Ṣé aríran+ wà ní ibí yìí?” 12 Wọ́n ní: “Ó wà níbí. Ẹ wò ó, ó wà lọ́hùn-ún yẹn níwájú yín. Ẹ ṣe kíá, torí pé ó wà ní ìlú yìí lónìí, nítorí àwọn èèyàn máa rú ẹbọ+ lónìí ní ibi gíga.+ 13 Gbàrà tí ẹ bá ti wọ ìlú náà, ẹ máa rí i kó tó gòkè lọ sí ibi gíga láti jẹun. Àwọn èèyàn náà kò ní jẹun títí á fi dé, nítorí òun ló máa gbàdúrà* sí ẹbọ náà. Ẹ̀yìn ìyẹn ni àwọn tí a pè tó lè jẹun. Torí náà, ẹ tètè gòkè lọ, ẹ máa rí i.” 14 Ni wọ́n bá gòkè lọ sí ìlú náà. Bí wọ́n ṣe ń dé àárín ìlú náà, Sámúẹ́lì rèé tó ń bọ̀ wá pàdé wọn láti gòkè lọ sí ibi gíga.
15 Ní ọjọ́ tó ṣáájú ọjọ́ tí Sọ́ọ̀lù dé, Jèhófà ti sọ fún Sámúẹ́lì* pé: 16 “Ní ìwòyí ọ̀la, màá rán ọkùnrin kan láti ilẹ̀ Bẹ́ńjámínì sí ọ.+ Kí o fòróró yàn án ṣe aṣáájú lórí àwọn èèyàn mi Ísírẹ́lì,+ yóò sì gba àwọn èèyàn mi lọ́wọ́ àwọn Filísínì. Nítorí mo ti rí ìpọ́njú àwọn èèyàn mi, igbe ẹkún wọn sì ti dé ọ̀dọ̀ mi.”+ 17 Nígbà tí Sámúẹ́lì rí Sọ́ọ̀lù, Jèhófà sọ fún un pé: “Ọkùnrin tí mo sọ nípa rẹ̀ fún ọ nìyí pé, ‘Òun ló máa ṣàkóso àwọn èèyàn mi.’”*+
18 Ìgbà náà ni Sọ́ọ̀lù sún mọ́ Sámúẹ́lì ní àárín ẹnubodè, ó sì sọ pé: “Jọ̀wọ́, sọ fún mi, ibo ni ilé aríran wà?” 19 Sámúẹ́lì dá Sọ́ọ̀lù lóhùn pé: “Èmi ni aríran náà. Máa gòkè lọ níwájú mi sí ibi gíga, ẹ ó sì bá mi jẹun lónìí.+ Màá jẹ́ kí ẹ máa lọ láàárọ̀ ọ̀la, màá sì sọ gbogbo ohun tí o fẹ́ mọ̀* fún ọ. 20 Ní ti àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ tó sọ nù lọ́jọ́ mẹ́ta sẹ́yìn,+ má dààmú nípa wọn, nítorí wọ́n ti rí wọn. Ó ṣe tán, ta ló ni gbogbo ohun tó ṣeyebíye ní Ísírẹ́lì? Ǹjẹ́ kì í ṣe ìwọ àti gbogbo ilé bàbá rẹ ni?”+ 21 Ni Sọ́ọ̀lù bá dáhùn pé: “Ṣebí ọmọ Bẹ́ńjámínì tó kéré jù nínú àwọn ẹ̀yà Ísírẹ́lì ni mí,+ tó sì jẹ́ pé ìdílé mi kò já mọ́ nǹkan kan láàárín gbogbo ìdílé ẹ̀yà Bẹ́ńjámínì? Torí náà, kí nìdí tí o fi bá mi sọ irú ọ̀rọ̀ yìí?”
22 Lẹ́yìn náà, Sámúẹ́lì mú Sọ́ọ̀lù àti ìránṣẹ́ rẹ̀ wá sí gbọ̀ngàn ìjẹun, ó fi wọ́n sí àyè tó ṣe pàtàkì jù láàárín àwọn tí a pè. Nǹkan bí ọgbọ̀n (30) ọkùnrin ni wọ́n. 23 Sámúẹ́lì sọ fún alásè pé: “Mú ìpín tí mo fún ọ wá, èyí tí mo sọ fún ọ pé, ‘Fi í pa mọ́.’” 24 Ni alásè náà bá gbé ẹsẹ̀ ẹran àti àwọn ohun tó wà lórí rẹ̀ síwájú Sọ́ọ̀lù. Sámúẹ́lì sì sọ pé: “Ohun tí a tọ́jú dè ọ́ ló wà níwájú rẹ yìí. Jẹ ẹ́, nítorí àkókò pàtàkì yìí ni wọ́n ṣe tọ́jú rẹ̀ dè ọ́. Mo ti sọ fún wọn pé, ‘mò ń retí àwọn àlejò.’” Torí náà, Sọ́ọ̀lù bá Sámúẹ́lì jẹun ní ọjọ́ yẹn. 25 Lẹ́yìn náà, wọ́n sọ̀ kalẹ̀ láti ibi gíga+ lọ sí ìlú náà, ó sì ń bá Sọ́ọ̀lù sọ̀rọ̀ ní orí ilé. 26 Wọ́n dìde ní kùtùkùtù, nígbà tí ilẹ̀ sì mọ́, Sámúẹ́lì pe Sọ́ọ̀lù ní orí ilé pé: “Múra, kí n lè sìn ọ́ dé ọ̀nà.” Torí náà, Sọ́ọ̀lù múra, òun àti Sámúẹ́lì sì jáde síta. 27 Bí wọ́n ṣe ń sọ̀ kalẹ̀ lọ sí ẹ̀yìn ìlú náà, Sámúẹ́lì sọ fún Sọ́ọ̀lù pé: “Sọ fún ìránṣẹ́+ yìí pé kó kọjá síwájú wa,” torí náà, ó lọ síwájú. “Àmọ́ ìwọ, dúró sí ibí yìí, kí n lè sọ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fún ọ.”
10 Ìgbà náà ni Sámúẹ́lì mú ṣágo* òróró, ó sì da òróró inú rẹ̀ sórí Sọ́ọ̀lù.+ Ó fi ẹnu kò ó lẹ́nu, ó sì sọ pé: “Ǹjẹ́ Jèhófà kò ti fòróró yàn ọ́ ṣe aṣáájú+ lórí ogún rẹ̀?+ 2 Tí o bá ti kúrò lọ́dọ̀ mi lónìí, wàá rí ọkùnrin méjì nítòsí ibojì Réṣẹ́lì+ ní ìpínlẹ̀ Bẹ́ńjámínì tó wà ní Sélésà, wọ́n á sì sọ fún ọ pé, ‘A ti rí àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ tí o wá lọ, bàbá rẹ kò tiẹ̀ ronú nípa àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà+ mọ́, àmọ́ ní báyìí ó ti ń dààmú nípa yín. Ó sọ pé: “Kí ni màá ṣe nípa ọmọ mi?”’ 3 Kí o sì lọ láti ibẹ̀ títí wàá fi dé ìdí igi ńlá tó wà ní Tábórì, ibẹ̀ ni wàá ti pàdé àwọn ọkùnrin mẹ́ta tó ń lọ sọ́dọ̀ Ọlọ́run tòótọ́ ní Bẹ́tẹ́lì,+ èkíní fa ọmọ ewúrẹ́ mẹ́ta dání, èkejì kó ìṣù búrẹ́dì mẹ́ta lọ́wọ́, ìkẹta sì gbé ìṣà wáìnì ńlá kan. 4 Wọ́n á béèrè àlàáfíà rẹ, wọ́n á sì fún ọ ní ìṣù búrẹ́dì méjì, kí o gbà á lọ́wọ́ wọn. 5 Lẹ́yìn náà, wàá dé òkè Ọlọ́run tòótọ́, níbi tí àwùjọ kan lára àwọn ọmọ ogun Filísínì wà. Tí o bá dé inú ìlú náà, wàá pàdé àwùjọ àwọn wòlíì tó ń sọ̀ kalẹ̀ bọ̀ láti ibi gíga, àwọn tó ń lo ohun ìkọrin olókùn tín-ín-rín àti ìlù tanboríìnì àti fèrè àti háàpù wà níwájú wọn, bí wọ́n ti ń sọ àsọtẹ́lẹ̀. 6 Ẹ̀mí Jèhófà yóò fún ọ lágbára,+ wàá máa sọ tẹ́lẹ̀ pẹ̀lú wọn, wàá sì yàtọ̀ sí ẹni tí o jẹ́ tẹ́lẹ̀.+ 7 Nígbà tí àmì wọ̀nyí bá ṣẹlẹ̀, ṣe gbogbo ohun tí o bá lè ṣe, torí pé Ọlọ́run tòótọ́ wà pẹ̀lú rẹ. 8 Lẹ́yìn náà, lọ sí Gílígálì+ kí n tó dé, màá sì wá bá ọ níbẹ̀ láti rú àwọn ẹbọ sísun àti àwọn ẹbọ ìrẹ́pọ̀. Ọjọ́ méje ni kí o fi dúró títí màá fi wá bá ọ. Ìgbà yẹn ni màá jẹ́ kí o mọ ohun ti wàá ṣe.”
9 Bí Sọ́ọ̀lù ṣe kúrò lọ́dọ̀ Sámúẹ́lì báyìí, Ọlọ́run bẹ̀rẹ̀ sí í yí i lọ́kàn pa dà kó lè di ẹni tó yàtọ̀, gbogbo àmì yìí sì ṣẹlẹ̀ ní ọjọ́ yẹn. 10 Nítorí náà, wọ́n lọ láti ibẹ̀ sórí òkè, àwùjọ àwọn wòlíì kan sì pàdé rẹ̀. Lọ́gán, ẹ̀mí Ọlọ́run fún un lágbára,+ ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í sọ tẹ́lẹ̀+ láàárín wọn. 11 Nígbà tí gbogbo àwọn tó mọ̀ ọ́n tẹ́lẹ̀ rí i tó ń sọ tẹ́lẹ̀ pẹ̀lú àwọn wòlíì, wọ́n ń sọ láàárín ara wọn pé: “Kí ló ṣẹlẹ̀ sí ọmọ Kíṣì? Ṣé Sọ́ọ̀lù náà wà lára àwọn wòlíì ni?” 12 Ni ọkùnrin kan láti ibẹ̀ bá sọ pé: “Ta tiẹ̀ ni bàbá wọn?” Torí náà, ó di ohun tí wọ́n ń sọ* pé: “Ṣé Sọ́ọ̀lù náà wà lára àwọn wòlíì ni?”+
13 Nígbà tí ó parí sísọ àsọtẹ́lẹ̀, ó wá sí ibi gíga. 14 Lẹ́yìn náà, arákùnrin bàbá Sọ́ọ̀lù sọ fún òun àti ìránṣẹ́ rẹ̀ pé: “Ibo ni ẹ lọ?” Ni ó bá sọ pé: “Àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ la wá lọ,+ àmọ́ a ò rí wọn, a wá lọ sọ́dọ̀ Sámúẹ́lì.” 15 Arákùnrin bàbá Sọ́ọ̀lù sọ pé: “Jọ̀ọ́, sọ fún mi, kí ni Sámúẹ́lì sọ fún yín?” 16 Sọ́ọ̀lù sọ fún arákùnrin bàbá rẹ̀ pé: “Ó sọ fún wa pé wọ́n ti rí àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà.” Àmọ́ Sọ́ọ̀lù kò sọ ohun tí Sámúẹ́lì sọ fún un nípa ipò ọba.
17 Sámúẹ́lì wá pe àwọn èèyàn náà jọ sọ́dọ̀ Jèhófà ní Mísípà,+ 18 ó sì sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé: “Ohun tí Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì sọ nìyí: ‘Èmi ló mú Ísírẹ́lì jáde kúrò ní Íjíbítì,+ tí mo sì gbà yín lọ́wọ́ Íjíbítì àti lọ́wọ́ gbogbo àwọn ìjọba tó ń ni yín lára. 19 Àmọ́ lónìí, ẹ ti kọ Ọlọ́run yín+ tó jẹ́ Olùgbàlà yín, tó gbà yín lọ́wọ́ gbogbo ibi àti wàhálà tó bá yín, ẹ sì sọ pé: “Àní sẹ́, fi ọba jẹ lórí wa.” Ní báyìí, ẹ dúró níwájú Jèhófà ní ẹ̀yà-ẹ̀yà àti ní ẹgbẹ̀rún-ẹgbẹ̀rún.’”*
20 Torí náà, Sámúẹ́lì ní kí gbogbo ẹ̀yà Ísírẹ́lì sún mọ́ tòsí,+ a sì mú ẹ̀yà Bẹ́ńjámínì.+ 21 Lẹ́yìn náà, ó ní kí ẹ̀yà Bẹ́ńjámínì sún mọ́ tòsí ní ìdílé-ìdílé, a sì mú ìdílé àwọn Mátírì. Níkẹyìn, a mú Sọ́ọ̀lù ọmọ Kíṣì.+ Àmọ́ nígbà tí wọ́n wá a lọ, wọn ò rí i. 22 Torí náà, wọ́n wádìí lọ́dọ̀ Jèhófà pé:+ “Ṣé ọkùnrin náà ò tíì dé ni?” Jèhófà dáhùn pé: “Òun ló fara pa mọ́ sáàárín ẹrù níbẹ̀ yẹn.” 23 Nítorí náà, wọ́n sáré lọ mú un wá láti ibẹ̀. Nígbà tó dúró láàárín àwọn èèyàn náà, kò sí ẹnì kankan lára àwọn èèyàn náà tó ga dé èjìká rẹ̀.+ 24 Sámúẹ́lì sọ fún gbogbo àwọn èèyàn náà pé: “Ṣé ẹ rí ẹni tí Jèhófà yàn,+ pé kò sí ẹnì kankan tó dà bíi rẹ̀ láàárín gbogbo èèyàn?” Gbogbo àwọn èèyàn náà bẹ̀rẹ̀ sí í kígbe pé: “Kí ẹ̀mí ọba ó gùn o!”
25 Sámúẹ́lì sọ fún àwọn èèyàn náà nípa ohun tí ọba lẹ́tọ̀ọ́ láti máa gbà lọ́wọ́ wọn,+ ó kọ ọ́ sínú ìwé kan, ó sì fi í lélẹ̀ níwájú Jèhófà. Lẹ́yìn náà, Sámúẹ́lì ní kí gbogbo àwọn èèyàn náà máa lọ, kí kálukú lọ sí ilé rẹ̀. 26 Sọ́ọ̀lù pẹ̀lú lọ sí ilé rẹ̀ ní Gíbíà, àwọn jagunjagun tí Jèhófà ti fọwọ́ tọ́ ọkàn wọn sì bá a lọ. 27 Àmọ́ àwọn aláìníláárí kan sọ pé: “Ṣé eléyìí ló máa gbà wá?”+ Torí náà, wọ́n pẹ̀gàn rẹ̀, wọn kò sì mú ẹ̀bùn èyíkéyìí wá fún un.+ Àmọ́ kò sọ ohunkóhun nípa rẹ̀.*
11 Nígbà náà, Náháṣì ará Ámónì+ wá pàgọ́ ti ìlú Jábéṣì ní Gílíádì. Gbogbo ọkùnrin Jábéṣì+ sì sọ fún Náháṣì pé: “Bá wa dá májẹ̀mú,* a ó sì sìn ọ́.” 2 Náháṣì ará Ámónì fún wọn lésì pé: “Ohun tí mo lè fi bá yín dá májẹ̀mú ni pé: Màá yọ ojú ọ̀tún ẹnì kọ̀ọ̀kan yín jáde kí n lè dójú ti gbogbo Ísírẹ́lì.” 3 Àwọn àgbààgbà ìlú Jábéṣì fún un lésì pé: “Fún wa ní ọjọ́ méje, ká lè rán àwọn òjíṣẹ́ sí gbogbo ìpínlẹ̀ Ísírẹ́lì. Tí a ò bá wá rí ẹni gbà wá, a ó fi ara wa lé ọ lọ́wọ́.” 4 Nígbà tó yá, àwọn òjíṣẹ́ náà dé Gíbíà+ ìlú Sọ́ọ̀lù,* wọ́n sọ ọ̀rọ̀ náà ní etí àwọn èèyàn, gbogbo àwọn èèyàn náà sì ń sunkún kíkankíkan.
5 Àmọ́ Sọ́ọ̀lù ń da ọ̀wọ́ ẹran bọ̀ láti pápá, ó sì sọ pé: “Kí ló ṣe àwọn èèyàn yìí? Kí ló ń pa wọ́n lẹ́kún?” Torí náà, wọ́n ròyìn ohun tí àwọn ọkùnrin Jábéṣì sọ fún un. 6 Bí Sọ́ọ̀lù ṣe gbọ́ ọ̀rọ̀ yìí, ẹ̀mí Ọlọ́run fún un lágbára,+ inú sì bí i gidigidi. 7 Torí náà, ó mú akọ màlúù méjì, ó gé wọn sí wẹ́wẹ́, ó sì fi wọ́n rán àwọn òjíṣẹ́ náà sí gbogbo ìpínlẹ̀ Ísírẹ́lì, wọ́n sọ pé: “Báyìí ni a máa ṣe sí màlúù ẹnikẹ́ni tí kò bá tẹ̀ lé Sọ́ọ̀lù àti Sámúẹ́lì!” Ìbẹ̀rù Jèhófà sì mú kí àwọn èèyàn náà jáde ní ìṣọ̀kan.* 8 Nígbà náà, ó ka iye wọn ní Bésékì, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì jẹ́ ọ̀kẹ́ mẹ́ẹ̀ẹ́dógún (300,000), àwọn ọkùnrin Júdà sì jẹ́ ọ̀kẹ́ kan ààbọ̀ (30,000). 9 Ni wọ́n bá sọ fún àwọn òjíṣẹ́ tó wá pé: “Ohun tí ẹ máa sọ fún àwọn èèyàn Jábéṣì ní Gílíádì nìyí, ‘Lọ́la, nígbà tí oòrùn bá mú, a máa gbà yín.’” Àwọn òjíṣẹ́ náà wá lọ sọ fún àwọn ọkùnrin Jábéṣì, inú wọn sì dùn gan-an. 10 Torí náà, àwọn ọkùnrin Jábéṣì sọ fún àwọn ọmọ Ámónì pé: “Lọ́la, a máa fi ara wa lé yín lọ́wọ́, kí ẹ ṣe ohun tó bá wù yín sí wa.”+
11 Ní ọjọ́ kejì, Sọ́ọ̀lù pín àwọn èèyàn náà sí àwùjọ mẹ́ta, wọ́n lọ sí àárín ibùdó náà ní àkókò ìṣọ́ òwúrọ̀,* wọ́n sì ń pa àwọn ọmọ Ámónì+ títí ọ̀sán fi pọ́n. Àwọn tó yè bọ́ fọ́n ká, tó fi jẹ́ pé kò sí méjì lára wọn tí ó wà pa pọ̀. 12 Àwọn èèyàn náà wá sọ fún Sámúẹ́lì pé: “Àwọn wo ló ń sọ pé, ‘Ṣé Sọ́ọ̀lù ló máa jẹ ọba lé wa lórí?’+ Ẹ fi wọ́n lé wa lọ́wọ́, a ó sì pa wọ́n.” 13 Àmọ́ Sọ́ọ̀lù sọ pé: “A ò gbọ́dọ̀ pa ẹnikẹ́ni lónìí yìí,+ torí pé òní ni Jèhófà gba Ísírẹ́lì sílẹ̀.”
14 Lẹ́yìn náà, Sámúẹ́lì sọ fún àwọn èèyàn náà pé: “Ẹ wá kí a lọ sí Gílígálì+ láti fìdí ipò ọba náà múlẹ̀.”+ 15 Torí náà, gbogbo àwọn èèyàn náà lọ sí Gílígálì, wọ́n sì fi Sọ́ọ̀lù jẹ ọba níwájú Jèhófà ní Gílígálì. Wọ́n rú àwọn ẹbọ ìrẹ́pọ̀ níbẹ̀ níwájú Jèhófà,+ Sọ́ọ̀lù àti gbogbo èèyàn Ísírẹ́lì sì ṣe ayẹyẹ pẹ̀lú ìdùnnú ńlá.+
12 Níkẹyìn, Sámúẹ́lì sọ fún gbogbo Ísírẹ́lì pé: “Ẹ wò ó, mo ti ṣe* gbogbo ohun tí ẹ ní kí n ṣe, mo sì ti fi ọba jẹ lé yín lórí.+ 2 Ọba tí á máa darí* yín rèé!+ Ní tèmi, mo ti darúgbó, mo sì ti hewú. Àwọn ọmọkùnrin mi wà lọ́dọ̀ yín,+ mo sì ti ń darí yín láti ìgbà èwe mi títí di òní yìí.+ 3 Èmi nìyí. Ẹ ta kò mí níwájú Jèhófà àti níwájú ẹni àmì òróró rẹ̀:+ Akọ màlúù tàbí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ta ni mo gbà rí?+ Àbí, ta ni mo lù ní jìbìtì tàbí tí mo ni lára? Ọwọ́ ta ni mo ti gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀,* tí màá fi gbé ojú mi sẹ́gbẹ̀ẹ́?+ Tó bá wà, màá san án pa dà fún yín.”+ 4 Wọ́n fèsì pé: “O ò lù wá ní jìbìtì, o ò ni wá lára, bẹ́ẹ̀ ni o ò gba ohunkóhun lọ́wọ́ ẹnikẹ́ni.” 5 Nítorí náà, ó sọ fún wọn pé: “Jèhófà ni ẹlẹ́rìí yín, ẹni àmì òróró rẹ̀ sì ṣe ẹlẹ́rìí lónìí yìí pé ẹ kò rí nǹkan kan tí ẹ máa fẹ̀sùn rẹ̀ kàn mí.”* Wọ́n fèsì pé: “Òun ni ẹlẹ́rìí.”
6 Sámúẹ́lì bá sọ fún àwọn èèyàn náà pé: “Jèhófà tó lo Mósè àti Áárónì, tó sì mú àwọn baba ńlá yín jáde kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì+ ni ẹlẹ́rìí. 7 Ní báyìí, ẹ dúró níwájú Jèhófà, màá bá yín ṣẹjọ́ nítorí gbogbo òdodo tí Jèhófà ti ṣe fún ẹ̀yin àti àwọn baba ńlá yín.
8 “Gbàrà tí Jékọ́bù dé sí Íjíbítì,+ tí àwọn baba ńlá yín sì bẹ̀rẹ̀ sí í ké pe Jèhófà fún ìrànlọ́wọ́,+ Jèhófà rán Mósè+ àti Áárónì, kí wọ́n lè mú àwọn baba ńlá yín jáde kúrò ní Íjíbítì, kí wọ́n sì mú kí wọ́n máa gbé ibí yìí.+ 9 Àmọ́ wọ́n gbàgbé Jèhófà Ọlọ́run wọn, ó sì tà wọ́n+ sọ́wọ́ Sísérà+ olórí àwọn ọmọ ogun Hásórì àti sọ́wọ́ àwọn Filísínì+ àti sọ́wọ́ ọba Móábù,+ wọ́n sì bá wọn jà. 10 Wọ́n ké pe Jèhófà fún ìrànlọ́wọ́,+ wọ́n sọ pé, ‘A ti dẹ́ṣẹ̀,+ nítorí a ti fi Jèhófà sílẹ̀ lọ sin àwọn Báálì+ àti àwọn ère Áṣítórétì;+ ní báyìí gbà wá lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá wa, kí a lè sìn ọ́.’ 11 Ìgbà náà ni Jèhófà rán Jerubáálì+ àti Bédánì àti Jẹ́fútà+ àti Sámúẹ́lì,+ ó sì gbà yín lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá tó yí yín ká, kí ẹ bàa lè máa gbé lábẹ́ ààbò.+ 12 Nígbà tí ẹ rí i pé Náháṣì+ ọba àwọn ọmọ Ámónì ti wá gbéjà kò yín, léraléra lẹ sọ fún mi pé, ‘Àní sẹ́, a ti pinnu láti ní ọba tiwa!’+ bó tilẹ̀ jẹ́ pé Jèhófà Ọlọ́run yín ni Ọba yín.+ 13 Ọba tí ẹ fẹ́ nìyí, ẹni tí ẹ béèrè. Ẹ wò ó! Jèhófà ti fi ọba jẹ lórí yín.+ 14 Tí ẹ bá bẹ̀rù Jèhófà,+ tí ẹ sì ń sìn ín,+ tí ẹ̀ ń ṣègbọràn sí ohùn rẹ̀,+ tí ẹ kò sì ṣọ̀tẹ̀ sí àṣẹ Jèhófà, tí ẹ̀yin àti ọba tí ó jẹ lórí yín ń tẹ̀ lé Jèhófà Ọlọ́run yín, á dáa fún yín. 15 Àmọ́ tí ẹ kò bá ṣègbọràn sí ohùn Jèhófà, tí ẹ kò sì pa àṣẹ Jèhófà mọ́, ọwọ́ Jèhófà yóò le mọ́ ẹ̀yin àti àwọn bàbá yín.+ 16 Ní báyìí, ẹ dúró, kí ẹ sì rí ohun ńlá yìí tí Jèhófà máa ṣe lójú yín. 17 Òní kọ́ ni ọjọ́ ìkórè àlìkámà* ni? Màá ké pe Jèhófà kí ó sán ààrá kí ó sì rọ òjò; kí ẹ wá mọ̀, kí ẹ sì lóye pé ohun búburú ni ẹ ṣe lójú Jèhófà nígbà tí ẹ ní kí ó fún yín ní ọba.”+
18 Ni Sámúẹ́lì bá ké pe Jèhófà, Jèhófà wá sán ààrá, ó sì rọ òjò ní ọjọ́ yẹn, tí gbogbo àwọn èèyàn náà fi bẹ̀rù Jèhófà àti Sámúẹ́lì gidigidi. 19 Gbogbo àwọn èèyàn náà sì sọ fún Sámúẹ́lì pé: “Gbàdúrà sí Jèhófà Ọlọ́run rẹ nítorí àwọn ìránṣẹ́ rẹ,+ nítorí a ò fẹ́ kú, torí pé a ti fi ohun búburú míì kún gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ wa bí a ṣe ní kí ó fún wa ní ọba.”
20 Torí náà, Sámúẹ́lì sọ fún àwọn èèyàn náà pé: “Ẹ má bẹ̀rù. Ẹ kúkú ti ṣe gbogbo ohun búburú yìí ná. Ẹ má ṣáà pa dà lẹ́yìn Jèhófà,+ kí ẹ sì máa fi gbogbo ọkàn yín sin Jèhófà.+ 21 Ẹ má ṣe lọ máa tẹ̀ lé àwọn ohun asán*+ tí kò ṣàǹfààní,+ tí kò sì lè gbani, nítorí pé asán* ni wọ́n jẹ́. 22 Jèhófà kò ní kọ àwọn èèyàn rẹ̀ sílẹ̀+ nítorí orúkọ ńlá rẹ̀+ àti nítorí pé Jèhófà ti pinnu láti fi yín ṣe èèyàn rẹ̀.+ 23 Ní tèmi, kò ṣeé gbọ́ sétí pé mo ṣẹ̀ sí Jèhófà pé mi ò gbàdúrà nítorí yín, èmi yóò sì máa fún yín ní ìtọ́ni ní ọ̀nà rere àti ọ̀nà tó tọ́. 24 Àfi kí ẹ bẹ̀rù Jèhófà,+ kí ẹ sì fi gbogbo ọkàn yín sìn ín ní òdodo,* ẹ̀yin náà ẹ wo àwọn ohun ńlá tí ó ti ṣe fún yín.+ 25 Àmọ́ bí ẹ bá fi ọ̀dájú ṣe ohun búburú, a ó gbá yín lọ,+ ẹ̀yin àti ọba yín.”+
13 Sọ́ọ̀lù jẹ́ ẹni ọdún . . .* nígbà tó jọba.+ Lẹ́yìn ọdún méjì tó ti ń jọba lórí Ísírẹ́lì, 2 Sọ́ọ̀lù yan ẹgbẹ̀rún mẹ́ta (3,000) èèyàn látinú Ísírẹ́lì; ẹgbẹ̀rún méjì (2,000) lára wọn wà pẹ̀lú Sọ́ọ̀lù ní Míkímáṣì àti ní agbègbè olókè Bẹ́tẹ́lì, ẹgbẹ̀rún kan (1,000) sì wà pẹ̀lú Jónátánì+ ní Gíbíà+ ti Bẹ́ńjámínì. Ó rán ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn tó ṣẹ́ kù lára àwọn èèyàn náà lọ sí àgọ́ wọn. 3 Nígbà náà, Jónátánì bá àwùjọ kan lára àwọn ọmọ ogun Filísínì+ tó wà ní Gébà+ jà, ó ṣẹ́gun wọn, àwọn Filísínì sì gbọ́. Ni Sọ́ọ̀lù bá ní kí wọ́n fun ìwo+ jákèjádò gbogbo ilẹ̀ náà, pé: “Kí gbogbo àwọn Hébérù gbọ́ o!” 4 Gbogbo Ísírẹ́lì sì gbọ́ ìròyìn pé: “Sọ́ọ̀lù ti ṣẹ́gun àwùjọ kan lára àwọn ọmọ ogun Filísínì, Ísírẹ́lì sì ti wá di ẹni ìkórìíra lójú àwọn Filísínì.” Torí náà, wọ́n pe àwọn èèyàn náà jọ sí Gílígálì láti tẹ̀ lé Sọ́ọ̀lù.+
5 Àwọn Filísínì pẹ̀lú kóra jọ láti bá Ísírẹ́lì jà, wọ́n ní ọ̀kẹ́ kan ààbọ̀ (30,000) kẹ̀kẹ́ ogun àti ẹgbẹ̀rún mẹ́fà (6,000) agẹṣin àti àwọn ọmọ ogun tó pọ̀ bí iyanrìn etí òkun;+ wọ́n jáde lọ, wọ́n sì tẹ̀ dó sí Míkímáṣì ní ìlà oòrùn Bẹti-áfénì.+ 6 Àwọn ọkùnrin Ísírẹ́lì rí i pé àwọn ti wọ ìjàngbọ̀n, torí pé ọwọ́ ọ̀tá le mọ́ wọn; ni àwọn èèyàn náà bá bẹ̀rẹ̀ sí í fara pa mọ́ sínú ihò àpáta,+ sínú kòtò, sínú pàlàpálá àpáta, ihò* abẹ́lẹ̀ àti àwọn kòtò omi. 7 Àwọn Hébérù kan tiẹ̀ sọdá Jọ́dánì lọ sí ilẹ̀ Gádì àti Gílíádì.+ Àmọ́ Sọ́ọ̀lù ṣì wà ní Gílígálì, jìnnìjìnnì sì ti bá gbogbo àwọn èèyàn tó ń tẹ̀ lé e. 8 Ọjọ́ méje ló fi ń dúró títí di àkókò tí Sámúẹ́lì dá,* àmọ́ Sámúẹ́lì kò wá sí Gílígálì, àwọn èèyàn sì ń tú ká mọ́ Sọ́ọ̀lù lórí. 9 Níkẹyìn, Sọ́ọ̀lù sọ pé: “Ẹ gbé ẹbọ sísun àti àwọn ẹbọ ìrẹ́pọ̀ wá fún mi.” Ó sì rú ẹbọ sísun náà.+
10 Àmọ́ gbàrà tó rú ẹbọ sísun náà tán, Sámúẹ́lì dé. Sọ́ọ̀lù bá jáde lọ pàdé rẹ̀, ó sì kí i káàbọ̀. 11 Sámúẹ́lì wá sọ pé: “Kí lo ṣe yìí?” Sọ́ọ̀lù fèsì pé: “Mo rí i pé àwọn èèyàn ti ń fi mí sílẹ̀,+ ìwọ náà ò sì dé ní àkókò tí o dá, àwọn Filísínì sì ń kóra jọ ní Míkímáṣì.+ 12 Ni mo bá sọ fún ara mi pé, ‘Àwọn Filísínì máa wá gbéjà kò mí ní Gílígálì, mi ò sì tíì wá ojú rere Jèhófà.’* Ìdí nìyẹn tí mo fi rí i pé ó pọn dandan kí n rú ẹbọ sísun náà.”
13 Ni Sámúẹ́lì bá sọ fún Sọ́ọ̀lù pé: “Ìwà òmùgọ̀ lo hù. O ò ṣègbọràn sí àṣẹ tí Jèhófà Ọlọ́run rẹ pa fún ọ.+ Ká ní o ṣe bẹ́ẹ̀ ni, Jèhófà ì bá fìdí ìjọba rẹ múlẹ̀ lórí Ísírẹ́lì títí láé. 14 Àmọ́ ní báyìí, ìjọba rẹ kò ní pẹ́.+ Jèhófà máa wá ọkùnrin kan tí ọkàn rẹ̀ fẹ́,+ Jèhófà sì máa yàn án ṣe aṣáájú lórí àwọn èèyàn rẹ̀,+ nítorí pé o ò ṣègbọràn sí ohun tí Jèhófà pa láṣẹ fún ọ.”+
15 Ìgbà náà ni Sámúẹ́lì dìde, ó sì bá tiẹ̀ lọ láti Gílígálì sí Gíbíà ti Bẹ́ńjámínì, Sọ́ọ̀lù sì ka àwọn èèyàn náà; àwọn tó ṣẹ́ kù sọ́dọ̀ rẹ̀ tó nǹkan bí ọgọ́rùn-ún mẹ́fà (600) ọkùnrin.+ 16 Sọ́ọ̀lù àti Jónátánì ọmọ rẹ̀ pẹ̀lú àwọn èèyàn tó ṣẹ́ kù sọ́dọ̀ wọn ń gbé ní Gébà+ ti Bẹ́ńjámínì, àwọn Filísínì sì ti pàgọ́ sí Míkímáṣì.+ 17 Agbo àwọn akónilẹ́rù máa ń jáde ogun láti ibùdó àwọn Filísínì ní àwùjọ mẹ́ta. Àwùjọ kan á yíjú sí ojú ọ̀nà tó lọ sí Ọ́fírà, sí ilẹ̀ Ṣúálì; 18 àwùjọ kejì á yíjú sí ojú ọ̀nà Bẹti-hórónì;+ àwùjọ kẹta á sì yíjú sí ojú ọ̀nà tó lọ sí ààlà tó dojú kọ àfonífojì Sébóímù, lápá aginjù.
19 Ní àkókò yẹn, kò sí alágbẹ̀dẹ kankan ní gbogbo ilẹ̀ Ísírẹ́lì, nítorí àwọn Filísínì ti sọ pé: “Kí àwọn Hébérù má bàa rọ idà tàbí ọ̀kọ̀.” 20 Gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní láti lọ sọ́dọ̀ àwọn Filísínì kí wọ́n lè pọ́n abẹ ohun ìtúlẹ̀ wọn, jígà wọn, àáké wọn tàbí dòjé wọn. 21 Iye tí wọ́n fi ń pọ́n ohun èlò kọ̀ọ̀kan jẹ́ píìmù* kan tí wọ́n bá fẹ́ pọ́n àwọn abẹ ìtúlẹ̀, jígà, àwọn ohun èlò eléyín mẹ́ta, àáké tàbí tí wọ́n bá fẹ́ de ọ̀pá kẹ́sẹ́ màlúù pinpin. 22 Ní ọjọ́ ogun, kò sí idà tàbí ọ̀kọ̀ lọ́wọ́ ìkankan lára àwọn tó wà pẹ̀lú Sọ́ọ̀lù àti Jónátánì;+ Sọ́ọ̀lù àti Jónátánì ọmọ rẹ̀ nìkan ló ní àwọn ohun ìjà.
23 Lákòókò yẹn, àwùjọ kan lára àwọn ọmọ ogun Filísínì* ti jáde lọ sí ọ̀nà àfonífojì tóóró tó wà ní Míkímáṣì.+
14 Lọ́jọ́ kan, Jónátánì+ ọmọ Sọ́ọ̀lù sọ fún ìránṣẹ́ tó ń bá a gbé àwọn ohun ìjà rẹ̀ pé: “Wá, jẹ́ ká sọdá sọ́dọ̀ àwùjọ ọmọ ogun Filísínì tó wà ní àdádó lódìkejì.” Àmọ́ kò sọ fún bàbá rẹ̀. 2 Sọ́ọ̀lù ń gbé ní ẹ̀yìn ìlú Gíbíà+ lábẹ́ igi pómégíránétì tó wà ní Mígírónì, àwọn tó sì wà pẹ̀lú rẹ̀ jẹ́ nǹkan bí ọgọ́rùn-ún mẹ́fà (600) ọkùnrin.+ 3 (Áhíjà ọmọ Áhítúbù,+ arákùnrin Íkábódì,+ ọmọ Fíníhásì,+ ọmọ Élì,+ àlùfáà Jèhófà ní Ṣílò+ tó ń wọ éfódì,+ sì wà pẹ̀lú wọn.) Àwọn èèyàn náà ò sì mọ̀ pé Jónátánì ti lọ. 4 Àpáta tó dà bí eyín wà lápá ọ̀tún àti lápá òsì ọ̀nà tí Jónátánì fẹ́ gbà kọjá lọ bá àwùjọ ọmọ ogun Filísínì tó wà ní àdádó, orúkọ àpáta kìíní ni Bósésì, ti ìkejì sì ni Sénè. 5 Èkíní jẹ́ òpó ní àríwá, ó dojú kọ Míkímáṣì, ìkejì sì wà ní gúúsù, ó dojú kọ Gébà.+
6 Nítorí náà, Jónátánì sọ fún ìránṣẹ́ tó ń bá a gbé ìhámọ́ra pé: “Wá, jẹ́ ká sọdá lọ sọ́dọ̀ àwùjọ ọmọ ogun aláìdádọ̀dọ́*+ tó wà ní àdádó yìí. Bóyá Jèhófà yóò ràn wá lọ́wọ́, nítorí kò sí ohun tó lè dí Jèhófà lọ́wọ́ láti gbani là, ì báà jẹ́ nípasẹ̀ àwọn tó pọ̀ tàbí àwọn díẹ̀.”+ 7 Ni ẹni tó ń gbé ìhámọ́ra rẹ̀ bá sọ fún un pé: “Ṣe ohun tí ọkàn rẹ bá sọ pé kí o ṣe. Yíjú sí ibi tí o bá fẹ́, màá sì tẹ̀ lé ọ lọ sí ibikíbi tí ọkàn rẹ bá sọ.” 8 Jónátánì bá sọ pé: “A máa sọdá lọ sọ́dọ̀ àwọn ọkùnrin náà, a ó sì fi ara wa hàn wọ́n. 9 Tí wọ́n bá sọ fún wa pé, ‘Ẹ dúró títí a ó fi wá bá yín!’ a ó dúró sí ibi tí a wà, a ò sì ní lọ bá wọn. 10 Ṣùgbọ́n tí wọ́n bá sọ pé, ‘Ẹ wá bá wa jà!’ a ó lọ, nítorí Jèhófà yóò fi wọ́n lé wa lọ́wọ́. Èyí á sì jẹ́ àmì fún wa.”+
11 Lẹ́yìn ìyẹn, àwọn méjèèjì fi ara wọn han àwùjọ ọmọ ogun Filísínì tó wà ní àdádó. Àwọn Filísínì sì sọ pé: “Àwọn Hébérù ti ń jáde bọ̀ látinú àwọn ihò tí wọ́n sá pa mọ́ sí.”+ 12 Torí náà, àwọn ọkùnrin ogun tó wà ní àdádó náà sọ fún Jónátánì àti ẹni tó ń gbé ìhámọ́ra rẹ̀ pé: “Ẹ wá bá wa, a ó sì kọ́ yín lọ́gbọ́n!”+ Ní kíá, Jónátánì sọ fún ẹni tó ń gbé ìhámọ́ra rẹ̀ pé: “Tẹ̀ lé mi, torí pé Jèhófà yóò fi wọ́n lé Ísírẹ́lì lọ́wọ́.”+ 13 Jónátánì wá fi ọwọ́ àti ẹsẹ̀ rẹ̀ gòkè, ẹni tó ń gbé ìhámọ́ra rẹ̀ sì tẹ̀ lé e; Jónátánì sì bẹ̀rẹ̀ sí í ṣá àwọn Filísínì balẹ̀, ẹni tó ń gbé ìhámọ́ra rẹ̀ sì ń pa wọ́n bọ̀ lẹ́yìn rẹ̀. 14 Nígbà tí Jónátánì àti ẹni tó ń gbé ìhámọ́ra rẹ̀ kọ́kọ́ lọ jà, wọ́n pa nǹkan bí ogún (20) ọkùnrin láàárín nǹkan bí ìdajì éékà kan.*
15 Nígbà náà, jìnnìjìnnì bá àwọn tó wà ní ibùdó inú pápá àti gbogbo àwọn tó wà lára àwùjọ ọmọ ogun tó wà ní àdádó, ẹ̀rù sì ba agbo ọmọ ogun akónilẹ́rù.+ Ilẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í mì tìtì, Ọlọ́run sì mú kí jìnnìjìnnì bá wọn. 16 Àwọn olùṣọ́ Sọ́ọ̀lù ní Gíbíà+ ti Bẹ́ńjámínì wá rí i pé rúkèrúdò náà ti ń dé ibi gbogbo.+
17 Sọ́ọ̀lù sọ fún àwọn tó wà pẹ̀lú rẹ̀ pé: “Ẹ jọ̀wọ́, ẹ ka iye àwọn èèyàn, kí ẹ sì mọ ẹni tó ti kúrò lọ́dọ̀ wa.” Nígbà tí wọ́n kà wọ́n, wọ́n rí i pé Jónátánì àti ẹni tó ń gbé ìhámọ́ra rẹ̀ kò sí níbẹ̀. 18 Sọ́ọ̀lù wá sọ fún Áhíjà pé:+ “Gbé Àpótí Ọlọ́run tòótọ́ sún mọ́ tòsí!” (Torí pé Àpótí Ọlọ́run tòótọ́ wà pẹ̀lú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní àkókò yẹn.*) 19 Bí Sọ́ọ̀lù ṣe ń bá àlùfáà náà sọ̀rọ̀ lọ́wọ́, rúkèrúdò tó wà ní ibùdó àwọn Filísínì ń pọ̀ sí i. Ni Sọ́ọ̀lù bá sọ fún àlùfáà náà pé: “Dáwọ́ ohun tí ò ń ṣe dúró.”* 20 Torí náà, Sọ́ọ̀lù àti gbogbo àwọn èèyàn tó wà pẹ̀lú rẹ̀ kóra jọ, wọ́n sì jáde lọ sí ojú ogun náà, ibẹ̀ ni wọ́n ti rí i tí àwọn Filísínì dojú idà kọ ara wọn, ìdàrúdàpọ̀ náà sì pọ̀ gan-an. 21 Bákan náà, àwọn Hébérù tí wọ́n ti gbè sẹ́yìn àwọn Filísínì tẹ́lẹ̀, tí wọ́n sì ti bá wọn wá sínú ibùdó wá ń pa dà sọ́dọ̀ Ísírẹ́lì lábẹ́ Sọ́ọ̀lù àti Jónátánì. 22 Gbogbo àwọn ọkùnrin Ísírẹ́lì tí wọ́n fara pa mọ́+ sí agbègbè olókè Éfúrémù gbọ́ pé àwọn Filísínì ti fẹsẹ̀ fẹ, ni àwọn náà bá bẹ̀rẹ̀ sí í lépa wọn lọ lójú ogun náà. 23 Torí náà, Jèhófà gba Ísírẹ́lì là lọ́jọ́ yẹn,+ ogun náà sì lọ títí dé Bẹti-áfénì.+
24 Àmọ́, ó ti rẹ àwọn ọkùnrin Ísírẹ́lì tẹnutẹnu ní ọjọ́ yẹn, torí Sọ́ọ̀lù ti mú kí àwọn èèyàn náà búra pé: “Ègún ni fún ẹni tó bá jẹ oúnjẹ* kankan kó tó di ìrọ̀lẹ́ àti kó tó di ìgbà tí màá gbẹ̀san lára àwọn ọ̀tá mi!” Torí náà, kò sí ẹnì kankan nínú àwọn èèyàn náà tí ó fi oúnjẹ kan ẹnu.+
25 Gbogbo àwọn èèyàn* náà dé inú igbó, oyin sì wà lórí ilẹ̀. 26 Nígbà tí àwọn èèyàn náà wọnú igbó náà, wọ́n rí oyin tó ń kán tótó, àmọ́ kò sí ẹni tó jẹ́ fi oyin náà kan ẹnu, torí pé wọ́n bẹ̀rù ìbúra náà. 27 Àmọ́ Jónátánì kò tíì gbọ́ pé bàbá rẹ̀ ti mú kí àwọn èèyàn náà búra,+ ni ó bá na ọ̀pá ọwọ́ rẹ̀ jáde, ó sì ti orí rẹ̀ bọ afárá oyin náà. Nígbà tí ó fi kan ẹnu, ara rẹ̀ mókun.* 28 Ni ọ̀kan lára àwọn èèyàn náà bá sọ pé: “Bàbá rẹ mú kí àwọn èèyàn búra lọ́nà tó lágbára pé, ‘Ègún ni fún ẹni tó bá jẹ oúnjẹ lónìí!’+ Ìdí nìyẹn tó fi rẹ àwọn èèyàn náà tẹnutẹnu.” 29 Àmọ́ Jónátánì sọ pé: “Bàbá mi ti kó wàhálà ńlá* bá ilẹ̀ yìí. Ẹ wo bí ara mi ṣe mókun* nítorí oyin díẹ̀ tí mo fi kan ẹnu. 30 Ì bá dáa gan-an ká ní pé àwọn èèyàn náà ti jẹun bó ṣe wù wọ́n+ lónìí látinú ẹrù àwọn ọ̀tá wọn tí wọ́n rí kó! Àwọn Filísínì tí wọ́n ì bá pa ì bá sì pọ̀ gan-an ju èyí lọ.”
31 Ní ọjọ́ yẹn, wọ́n ń pa àwọn Filísínì láti Míkímáṣì títí dé Áíjálónì,+ ó sì rẹ àwọn èèyàn náà gan-an. 32 Àwọn èèyàn náà sì bẹ̀rẹ̀ sí í fi wàdùwàdù kó ẹrù ogun, wọ́n mú àgùntàn àti màlúù àti ọmọ màlúù, wọ́n pa wọ́n lórí ilẹ̀, wọ́n sì ń jẹ ẹran náà tẹ̀jẹ̀tẹ̀jẹ̀.+ 33 Torí náà, wọ́n sọ fún Sọ́ọ̀lù pé: “Wò ó! Àwọn èèyàn yìí ń dẹ́ṣẹ̀ sí Jèhófà nítorí wọ́n ń jẹ ẹran tẹ̀jẹ̀tẹ̀jẹ̀.”+ Ni ó bá sọ pé: “Ẹ ti hùwà àìṣòótọ́. Ẹ yí òkúta ńlá kan wá sọ́dọ̀ mi kíákíá.” 34 Sọ́ọ̀lù bá sọ pé: “Ẹ lọ sáàárín àwọn èèyàn, kí ẹ sì sọ fún wọn pé, ‘Kí kálukú yín mú akọ màlúù rẹ̀ àti àgùntàn rẹ̀ wá, kí ó pa á níbí, lẹ́yìn náà kí ó jẹ ẹ́. Ẹ má jẹ ẹran tẹ̀jẹ̀tẹ̀jẹ̀+ kí ẹ má bàa ṣẹ̀ sí Jèhófà.’” Nípa bẹ́ẹ̀, kálukú wọn mú akọ màlúù rẹ̀ wá ní òru ọjọ́ yẹn, wọ́n sì pa á níbẹ̀. 35 Sọ́ọ̀lù sì mọ pẹpẹ kan fún Jèhófà.+ Pẹpẹ yìí ló kọ́kọ́ mọ fún Jèhófà.
36 Lẹ́yìn náà, Sọ́ọ̀lù sọ pé: “Ẹ jẹ́ ká lọ gbéjà ko àwọn Filísínì ní òru, kí a sì kó nǹkan wọn títí ilẹ̀ á fi mọ́. A ò ní ṣẹ́ ẹyọ ẹnì kan kù nínú wọn.” Wọ́n fèsì pé: “Ṣe ohun tó bá dára ní ojú rẹ.” Nígbà náà, àlùfáà sọ pé: “Ẹ jẹ́ ká wádìí lọ́dọ̀ Ọlọ́run tòótọ́ níbí yìí.”+ 37 Sọ́ọ̀lù béèrè lọ́wọ́ Ọlọ́run pé: “Ṣé kí n lọ bá àwọn Filísínì?+ Ṣé wàá fi wọ́n lé Ísírẹ́lì lọ́wọ́?” Àmọ́ Ọlọ́run kò dá a lóhùn ní ọjọ́ yẹn. 38 Sọ́ọ̀lù wá sọ pé: “Ẹ máa bọ̀, gbogbo ẹ̀yin ìjòyè àwọn èèyàn, ẹ wádìí, kí a lè mọ ẹni tó dá ẹ̀ṣẹ̀ lónìí. 39 Nítorí bí Jèhófà, ẹni tí ó gba Ísírẹ́lì ti wà láàyè, kódà ì báà jẹ́ Jónátánì ọmọ mi ni, ó gbọ́dọ̀ kú.” Àmọ́ kò sí ìkankan lára àwọn èèyàn náà tó dá a lóhùn. 40 Lẹ́yìn náà, ó sọ fún gbogbo Ísírẹ́lì pé: “Ẹ̀yin, ẹ dúró sẹ́gbẹ̀ẹ́ kan, èmi àti Jónátánì ọmọ mi á wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ kejì.” Ni àwọn èèyàn náà bá sọ fún Sọ́ọ̀lù pé: “Ṣe ohun tó bá dára ní ojú rẹ.”
41 Sọ́ọ̀lù wá sọ fún Jèhófà pé: “Ọlọ́run Ísírẹ́lì, fi Túmímù+ dáhùn!” Ni Túmímù bá mú Jónátánì àti Sọ́ọ̀lù, àwọn èèyàn náà sì bọ́. 42 Sọ́ọ̀lù wá sọ pé: “Ẹ ṣẹ́ kèké+ kí a lè mọ ẹni tó jẹ́ láàárín èmi àti Jónátánì ọmọ mi.” Túmímù sì mú Jónátánì. 43 Ni Sọ́ọ̀lù bá sọ fún Jónátánì pé: “Sọ fún mi, kí lo ṣe?” Jónátánì wá sọ fún un pé: “Mo kàn fi oyin díẹ̀ tó wà lórí ọ̀pá mi kan ẹnu ni o.+ Èmi rèé! Mo ṣe tán láti kú!”
44 Ni Sọ́ọ̀lù bá sọ pé: “Kí Ọlọ́run fi ìyà jẹ mí gan-an tó ò bá ní kú, Jónátánì.”+ 45 Ṣùgbọ́n àwọn èèyàn náà sọ fún Sọ́ọ̀lù pé: “Ṣé ó yẹ kí Jónátánì kú, ẹni tó mú ìṣẹ́gun* ńlá+ wá fún Ísírẹ́lì? Kò ṣeé gbọ́ sétí! Bí Jèhófà ti wà láàyè, ẹyọ kan nínú irun orí rẹ̀ kò ní bọ́ sílẹ̀, nítorí Ọlọ́run lọ́wọ́ sí gbogbo ohun tó ṣe lónìí yìí.”+ Bí àwọn èèyàn náà ṣe gba Jónátánì sílẹ̀* nìyẹn, kò sì kú.
46 Torí náà, Sọ́ọ̀lù dẹ̀yìn lẹ́yìn àwọn Filísínì, àwọn Filísínì sì lọ sí agbègbè wọn.
47 Sọ́ọ̀lù fìdí ìjọba rẹ̀ múlẹ̀ lórí Ísírẹ́lì, ó sì bá gbogbo ọ̀tá rẹ̀ jà níbi gbogbo, ó bá àwọn ọmọ Móábù+ àti àwọn ọmọ Ámónì+ jà, ó tún bá àwọn ọmọ Édómù+ àti àwọn ọba Sóbà+ pẹ̀lú àwọn Filísínì+ jà; ó sì ń ṣẹ́gun níbikíbi tó bá lọ. 48 Ó fi ìgboyà jà, ó ṣẹ́gun àwọn ọmọ Ámálékì,+ ó sì gba Ísírẹ́lì lọ́wọ́ àwọn tó ń kó ohun ìní wọn lọ.
49 Àwọn ọmọkùnrin Sọ́ọ̀lù ni Jónátánì, Íṣífì àti Maliki-ṣúà.+ Ó ní ọmọbìnrin méjì; èyí ẹ̀gbọ́n ń jẹ́ Mérábù,+ àbúrò rẹ̀ sì ń jẹ́ Míkálì.+ 50 Orúkọ ìyàwó rẹ̀ ni Áhínóámù ọmọ Áhímáásì. Orúkọ olórí àwọn ọmọ ogun rẹ̀ ni Ábínérì+ ọmọ Nérì tó jẹ́ arákùnrin bàbá Sọ́ọ̀lù. 51 Kíṣì+ ni bàbá Sọ́ọ̀lù, Nérì+ bàbá Ábínérì sì ni ọmọ Ábíélì.
52 Ogun tó le ni àwọn Filísínì dojú kọ nígbà ayé Sọ́ọ̀lù.+ Tí Sọ́ọ̀lù bá sì rí ọkùnrin èyíkéyìí tó lágbára tàbí tó láyà, á gbà á síṣẹ́ ogun.+
15 Nígbà náà, Sámúẹ́lì sọ fún Sọ́ọ̀lù pé: “Jèhófà rán mi láti fòróró yàn ọ́ ṣe ọba lórí àwọn èèyàn rẹ̀ Ísírẹ́lì;+ ní báyìí, gbọ́ ohun tí Jèhófà fẹ́ sọ.+ 2 Ohun tí Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun sọ nìyí: ‘Màá pe àwọn ọmọ Ámálékì wá jíhìn nítorí ohun tí wọ́n ṣe sí Ísírẹ́lì bí wọ́n ṣe gbéjà kò ó nígbà tó ń jáde bọ̀ láti Íjíbítì.+ 3 Ní báyìí, lọ ṣá àwọn ọmọ Ámálékì+ balẹ̀, kí o sì pa wọ́n run pátápátá+ pẹ̀lú gbogbo ohun tí wọ́n ní. O ò gbọ́dọ̀ dá wọn sí;* ṣe ni kí o pa gbogbo wọn,+ ọkùnrin àti obìnrin, ọmọdé àti ọmọ jòjòló, akọ màlúù àti àgùntàn, ràkúnmí àti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́.’”+ 4 Sọ́ọ̀lù pe àwọn èèyàn náà jọ, ó sì kà wọ́n ní Téláímù: Wọ́n jẹ́ ọ̀kẹ́ mẹ́wàá (200,000) ọmọ ogun tó ń fẹsẹ̀ rìn àti ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá (10,000) ọkùnrin Júdà.+
5 Sọ́ọ̀lù lọ títí dé ìlú Ámálékì, ó sì lúgọ sẹ́gbẹ̀ẹ́ àfonífojì. 6 Sọ́ọ̀lù wá sọ fún àwọn Kénì pé:+ “Ẹ jáde kúrò láàárín àwọn ọmọ Ámálékì, kí n má bàa gbá yín lọ pẹ̀lú wọn.+ Nítorí ẹ fi ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ hàn sí gbogbo ọmọ Ísírẹ́lì+ nígbà tí wọ́n jáde kúrò ní Íjíbítì.” Torí náà, àwọn Kénì kúrò ní àárín àwọn ọmọ Ámálékì. 7 Lẹ́yìn ìyẹn, Sọ́ọ̀lù pa àwọn ọmọ Ámálékì+ láti Háfílà+ títí dé Ṣúrì,+ tó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ Íjíbítì. 8 Ó mú Ágágì+ ọba Ámálékì láàyè, àmọ́ ó fi idà pa gbogbo àwọn èèyàn tó ṣẹ́ kù run.+ 9 Ṣùgbọ́n Sọ́ọ̀lù àti àwọn ọmọ ogun rẹ̀ dá Ágágì sí* àti agbo ẹran tó dára jù, títí kan ọ̀wọ́ ẹran, àwọn ẹran àbọ́sanra, àwọn àgbò àti gbogbo ohun tó dára.+ Wọn ò fẹ́ pa wọ́n run. Àmọ́ wọ́n pa gbogbo nǹkan tí kò ní láárí, tí kò sì wúlò run.
10 Ìgbà náà ni Jèhófà bá Sámúẹ́lì sọ̀rọ̀, ó ní: 11 “Ó dùn mí* pé mo fi Sọ́ọ̀lù jọba, torí ó ti pa dà lẹ́yìn mi, kò sì ṣe ohun tí mo sọ.”+ Inú Sámúẹ́lì bà jẹ́ gan-an, ó sì ń ké pe Jèhófà láti òru mọ́jú.+ 12 Nígbà tí Sámúẹ́lì dìde ní àárọ̀ kùtù láti lọ bá Sọ́ọ̀lù, wọ́n sọ fún Sámúẹ́lì pé: “Sọ́ọ̀lù ti lọ sí Kámẹ́lì,+ ó sì gbé ohun tí wọ́n á máa fi rántí rẹ̀ dúró síbẹ̀.+ Ó wá pa dà, ó sì gba Gílígálì lọ.” 13 Níkẹyìn, Sámúẹ́lì dé ọ̀dọ̀ rẹ̀, Sọ́ọ̀lù sì sọ fún un pé: “Kí Jèhófà bù kún ọ. Mo ti ṣe ohun tí Jèhófà sọ.” 14 Àmọ́ Sámúẹ́lì sọ pé: “Kí wá ni ohùn agbo ẹran tó ń dún yìí àti ohùn ọ̀wọ́ ẹran tí mò ń gbọ́ yìí?”+ 15 Ni Sọ́ọ̀lù bá sọ pé: “Ọ̀dọ̀ àwọn ọmọ Ámálékì ni wọ́n ti mú wọn wá, nítorí àwọn èèyàn náà dá agbo ẹran àti ọ̀wọ́ ẹran tó dára jù sí,* láti fi wọ́n rúbọ sí Jèhófà Ọlọ́run rẹ; àmọ́ a ti pa àwọn ohun tó ṣẹ́ kù run.” 16 Sámúẹ́lì bá sọ fún Sọ́ọ̀lù pé: “Ó tó! Jẹ́ kí n sọ ohun tí Jèhófà sọ fún mi lóru àná fún ọ.”+ Torí náà, ó sọ fún un pé: “Sọ ọ́!”
17 Sámúẹ́lì ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ, ó ní: “Ṣebí o ò já mọ́ nǹkan lójú ara rẹ+ nígbà tí a fi ọ́ ṣe olórí àwọn ẹ̀yà Ísírẹ́lì, tí Jèhófà sì fòróró yàn ọ́ ṣe ọba lórí Ísírẹ́lì?+ 18 Ẹ̀yìn náà ni Jèhófà rán ọ níṣẹ́, ó sọ pé, ‘Lọ pa àwọn ọmọ Ámálékì tó jẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀ run pátápátá.+ Bá wọn jà títí wàá fi pa wọ́n run.’+ 19 Kí ló dé tí o ò ṣègbọràn sí ohùn Jèhófà? Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe lo fi ojúkòkòrò kó nǹkan wọn,+ tí o sì ṣe ohun tó burú ní ojú Jèhófà!”
20 Sọ́ọ̀lù wá sọ fún Sámúẹ́lì pé: “Ṣebí mo ti ṣègbọràn sí ohùn Jèhófà! Mo lọ jíṣẹ́ tí Jèhófà rán mi, mo mú Ágágì ọba Ámálékì wá, mo sì pa àwọn ọmọ Ámálékì run pátápátá.+ 21 Àmọ́ àwọn èèyàn náà kó àgùntàn àti màlúù látinú ẹrù ogun, èyí tó dára jù nínú ohun tí wọ́n fẹ́ pa run, láti fi rúbọ sí Jèhófà Ọlọ́run rẹ ní Gílígálì.”+
22 Sámúẹ́lì wá sọ pé: “Ṣé àwọn ẹbọ sísun àti ẹbọ+ máa ń múnú Jèhófà dùn tó kéèyàn ṣègbọràn sí ohùn Jèhófà? Wò ó! Ṣíṣe ìgbọràn sàn ju ẹbọ,+ fífi etí sílẹ̀ sì sàn ju ọ̀rá+ àgbò; 23 nítorí ẹ̀ṣẹ̀ kan náà ni ìṣọ̀tẹ̀+ àti iṣẹ́ wíwò+ jẹ́, ọ̀kan náà sì ni kíkọjá àyè jẹ́ pẹ̀lú lílo agbára abàmì àti ìbọ̀rìṣà.* Nítorí o ti kọ ọ̀rọ̀ Jèhófà,+ òun náà ti kọ̀ ọ́ ní ọba.”+
24 Ìgbà náà ni Sọ́ọ̀lù sọ fún Sámúẹ́lì pé: “Mo ti ṣẹ̀, torí mo ti tẹ àṣẹ Jèhófà àti ọ̀rọ̀ rẹ lójú, nítorí mo bẹ̀rù àwọn èèyàn, mo sì fetí sí ohun tí wọ́n sọ. 25 Ní báyìí, jọ̀wọ́, dárí ẹ̀ṣẹ̀ mi jì mí, kí o sì bá mi pa dà kí n lè forí balẹ̀ fún Jèhófà.”+ 26 Àmọ́ Sámúẹ́lì sọ fún Sọ́ọ̀lù pé: “Mi ò ní bá ọ pa dà, nítorí o ti kọ ọ̀rọ̀ Jèhófà, Jèhófà sì ti kọ̀ ọ́ pé kí o má ṣe jẹ́ ọba lórí Ísírẹ́lì mọ́.”+ 27 Bí Sámúẹ́lì ṣe ń yíjú pa dà láti lọ, Sọ́ọ̀lù gbá etí aṣọ àwọ̀lékè rẹ̀ tí kò lápá mú, aṣọ náà bá fà ya. 28 Sámúẹ́lì wá sọ fún un pé: “Jèhófà ti fa ìṣàkóso Ísírẹ́lì ya kúrò lọ́wọ́ rẹ lónìí, yóò sì fún ọmọnìkejì rẹ tó sàn jù ọ́ lọ.+ 29 Yàtọ̀ síyẹn, Atóbilọ́lá Ísírẹ́lì+ kò ní jẹ́ parọ́+ tàbí kó yí ìpinnu rẹ̀ pa dà,* nítorí Òun kì í ṣe èèyàn tí á fi yí ìpinnu rẹ̀ pa dà.”*+
30 Ó wá sọ pé: “Mo ti ṣẹ̀. Àmọ́, jọ̀ọ́ bọlá fún mi níwájú àgbààgbà àwọn èèyàn mi àti níwájú Ísírẹ́lì. Bá mi pa dà, màá sì forí balẹ̀ fún Jèhófà Ọlọ́run rẹ.”+ 31 Torí náà, Sámúẹ́lì tẹ̀ lé Sọ́ọ̀lù pa dà, Sọ́ọ̀lù sì forí balẹ̀ fún Jèhófà. 32 Sámúẹ́lì wá sọ pé: “Ẹ mú Ágágì ọba Ámálékì sún mọ́ mi.” Ni ara bá ń ti Ágágì láti* lọ sọ́dọ̀ rẹ̀ nítorí Ágágì ń sọ lọ́kàn ara rẹ̀ pé: ‘Ó dájú pé ikú* ti yẹ̀ lórí mi.’ 33 Àmọ́ Sámúẹ́lì sọ pé: “Bí idà rẹ ṣe mú àwọn obìnrin ṣòfò ọmọ, bẹ́ẹ̀ ni ìyá rẹ á ṣe di ẹni tó ṣòfò ọmọ jù láàárín àwọn obìnrin.” Ni Sámúẹ́lì bá ṣá Ágágì sí wẹ́wẹ́ níwájú Jèhófà ní Gílígálì.+
34 Sámúẹ́lì gba Rámà lọ, Sọ́ọ̀lù sì lọ sí ilé rẹ̀ ní Gíbíà ìlú rẹ̀. 35 Títí Sámúẹ́lì fi kú, kò rí Sọ́ọ̀lù mọ́, ńṣe ni Sámúẹ́lì bẹ̀rẹ̀ sí í ṣọ̀fọ̀ nítorí Sọ́ọ̀lù.+ Ó sì dun Jèhófà* pé ó fi Sọ́ọ̀lù jẹ ọba lórí Ísírẹ́lì.+
16 Níkẹyìn, Jèhófà sọ fún Sámúẹ́lì pé: “Ìgbà wo lo máa ṣọ̀fọ̀ Sọ́ọ̀lù dà,+ ní báyìí tí mo ti kọ Sọ́ọ̀lù pé kí ó má ṣe jẹ́ ọba lórí Ísírẹ́lì mọ́?+ Rọ òróró sínú ìwo,+ kí o sì lọ. Màá rán ọ lọ sọ́dọ̀ Jésè+ ará Bẹ́tílẹ́hẹ́mù, nítorí mo ti yan ọ̀kan lára àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ láti jẹ́ ọba fún mi.”+ 2 Àmọ́ Sámúẹ́lì sọ pé: “Báwo ni màá ṣe lọ? Tí Sọ́ọ̀lù bá gbọ́ nípa rẹ̀, yóò pa mí.”+ Jèhófà fèsì pé: “Mú abo ọmọ màlúù kan dání, kí o sì sọ pé, ‘Mo wá rúbọ sí Jèhófà ni.’ 3 Pe Jésè síbi ẹbọ náà; màá sì jẹ́ kí o mọ ohun tí o máa ṣe. Kí o bá mi fòróró yan ẹni tí mo bá tọ́ka sí fún ọ.”+
4 Sámúẹ́lì ṣe ohun tí Jèhófà sọ. Nígbà tó dé Bẹ́tílẹ́hẹ́mù,+ ẹ̀rù ń ba àwọn àgbààgbà ìlú nígbà tí wọ́n wá pàdé rẹ̀, wọ́n sọ pé: “Ṣé àlàáfíà lo bá wá?” 5 Ó fèsì pé: “Àlàáfíà ni. Mo wá rúbọ sí Jèhófà ni. Ẹ ya ara yín sí mímọ́, kí ẹ sì bá mi lọ síbi ẹbọ náà.” Ó wá ya Jésè àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ sí mímọ́, lẹ́yìn náà ó pè wọ́n síbi ẹbọ náà. 6 Bí wọ́n ṣe wọlé, tí ó sì rí Élíábù,+ ó sọ pé: “Ó dájú pé ẹni àmì òróró Jèhófà ló dúró yìí.” 7 Ṣùgbọ́n Jèhófà sọ fún Sámúẹ́lì pé: “Má wo ìrísí rẹ̀ àti bí ó ṣe ga tó,+ torí pé mo ti kọ̀ ọ́. Nítorí ọ̀nà tí èèyàn gbà ń wo nǹkan kọ́ ni Ọlọ́run gbà ń wo nǹkan, torí pé ohun tí ó bá hàn síta ni èèyàn ń rí, ṣùgbọ́n Jèhófà ń rí ohun tó wà nínú ọkàn.”+ 8 Jésè bá pe Ábínádábù,+ ó sì ní kí ó kọjá níwájú Sámúẹ́lì, àmọ́ ó sọ pé: “Jèhófà kò yan eléyìí náà.” 9 Lẹ́yìn náà, Jésè mú Ṣámà wá,+ ṣùgbọ́n ó sọ pé: “Jèhófà kò yan eléyìí náà.” 10 Nítorí náà, Jésè mú kí méje lára àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ kọjá níwájú Sámúẹ́lì, àmọ́ Sámúẹ́lì sọ fún Jésè pé: “Jèhófà kò yan ìkankan lára wọn.”
11 Níkẹyìn, Sámúẹ́lì béèrè lọ́wọ́ Jésè pé: “Ṣé gbogbo àwọn ọmọkùnrin rẹ nìyí?” Ó fèsì pé: “Èyí tó kéré jù+ ṣì wà níta; ó kó àwọn àgùntàn lọ jẹ koríko.”+ Ni Sámúẹ́lì bá sọ fún Jésè pé: “Ní kí wọ́n lọ pè é wá, torí ó dìgbà tó bá dé ká tó jókòó láti jẹun.” 12 Torí náà, ó ránṣẹ́ pè é, ó sì mú un wọlé. Ọmọ náà pupa, ẹyinjú rẹ̀ mọ́ lóló, ó sì rẹwà gan-an.+ Ni Jèhófà bá sọ pé: “Dìde, fòróró yàn án, torí òun nìyí!”+ 13 Torí náà, Sámúẹ́lì mú ìwo tí òróró wà nínú rẹ̀,+ ó sì fòróró yàn án lójú àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀. Ẹ̀mí Jèhófà sì bẹ̀rẹ̀ sí í fún Dáfídì lágbára láti ọjọ́ náà lọ.+ Lẹ́yìn náà, Sámúẹ́lì dìde, ó sì gba Rámà lọ.+
14 Àmọ́ ní ti Sọ́ọ̀lù, ẹ̀mí Jèhófà ti kúrò lára rẹ̀,+ Jèhófà sì jẹ́ kí ẹ̀mí búburú máa dà á láàmú.+ 15 Àwọn ìránṣẹ́ Sọ́ọ̀lù bá sọ fún un pé: “O ò rí i pé Ọlọ́run ti ń jẹ́ kí ẹ̀mí búburú máa dà ọ́ láàmú. 16 Jọ̀ọ́, jẹ́ kí olúwa wa pàṣẹ fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ tó wà níwájú rẹ̀ pé kí wọ́n wá ọkùnrin tó mọ háàpù ta dáadáa.+ Ìgbàkígbà tí Ọlọ́run bá ti jẹ́ kí ẹ̀mí búburú dà ọ́ láàmú, yóò ta háàpù náà, ara rẹ á sì balẹ̀.” 17 Nítorí náà, Sọ́ọ̀lù sọ fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pé: “Ẹ jọ̀wọ́, ẹ bá mi wá ọkùnrin kan tó mọ háàpù ta dáadáa, kí ẹ sì mú un wá sọ́dọ̀ mi.”
18 Ọ̀kan lára àwọn ẹmẹ̀wà* sọ pé: “Wò ó! Mo ti rí bí ọ̀kan lára àwọn ọmọ Jésè ará Bẹ́tílẹ́hẹ́mù ṣe ń ta háàpù dáadáa, onígboyà ni, jagunjagun tó lákíkanjú sì ni.+ Ó mọ̀rọ̀ọ́ sọ, ó rẹwà,+ Jèhófà sì wà pẹ̀lú rẹ̀.”+ 19 Ni Sọ́ọ̀lù bá rán àwọn òjíṣẹ́ sí Jésè pé: “Fi Dáfídì ọmọ rẹ tó wà pẹ̀lú agbo ẹran ránṣẹ́ sí mi.”+ 20 Nítorí náà, Jésè gbé oúnjẹ àti wáìnì ìgò awọ kan pẹ̀lú ọmọ ewúrẹ́, ó dì wọ́n sórí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, ó sì fi wọ́n ránṣẹ́ pẹ̀lú Dáfídì ọmọ rẹ̀ sí Sọ́ọ̀lù. 21 Bí Dáfídì ṣe wá sọ́dọ̀ Sọ́ọ̀lù nìyẹn, tí ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe ìránṣẹ́ rẹ̀.+ Sọ́ọ̀lù wá nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ gan-an, ó sì yàn án pé kó máa gbé ìhámọ́ra òun. 22 Sọ́ọ̀lù ránṣẹ́ sí Jésè pé: “Jọ̀wọ́, jẹ́ kí Dáfídì máa ṣe ìránṣẹ́ mi nìṣó, torí ó ti rí ojú rere mi.” 23 Ìgbàkígbà tí Ọlọ́run bá ti jẹ́ kí ẹ̀mí búburú mú Sọ́ọ̀lù, Dáfídì á mú háàpù, á sì ta á, ìtura á bá Sọ́ọ̀lù, ara rẹ̀ á balẹ̀, ẹ̀mí búburú náà á sì fi í sílẹ̀.+
17 Àwọn Filísínì+ kó àwọn ọmọ ogun* wọn jọ láti jagun. Wọ́n kóra jọ sí Sókọ̀+ ti ilẹ̀ Júdà, wọ́n sì dó sí àárín Sókọ̀ àti Ásékà,+ ní Efesi-dámímù.+ 2 Sọ́ọ̀lù àti àwọn ọkùnrin Ísírẹ́lì kóra jọ, wọ́n pàgọ́ sí Àfonifojì* Élà,+ wọ́n sì tò lọ́wọ̀ọ̀wọ́ láti pàdé àwọn Filísínì. 3 Àwọn Filísínì wà lórí òkè ní ẹ̀gbẹ́ kan, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì wà lórí òkè ní ẹ̀gbẹ́ kejì, àfonífojì sì wà láàárín wọn.
4 Ni akọgun kan bá jáde láti ibùdó àwọn Filísínì, Gòláyátì ni orúkọ rẹ̀,+ ará Gátì ni,+ gíga rẹ̀ jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́fà àti ìbú àtẹ́lẹwọ́ kan.* 5 Ó dé akoto* bàbà sórí, ó sì wọ ẹ̀wù irin tí àwọn ìpẹ́ rẹ̀ gbẹ́nu léra. Ìwọ̀n ẹ̀wù irin bàbà+ náà jẹ́ ẹgbẹ̀rún márùn-ún (5,000) ṣékélì.* 6 Kóbìtà* bàbà wà ní ẹsẹ̀ rẹ̀, ó sì gbé ẹ̀ṣín*+ bàbà kọ́ èjìká rẹ̀. 7 Igi ọ̀kọ̀ rẹ̀ dà bí ọ̀pá àwọn ahunṣọ,*+ ìwọ̀n irin tí wọ́n fi ṣe aṣóró ọ̀kọ̀ rẹ̀ sì jẹ́ ọgọ́rùn-ún mẹ́fà (600) ṣékélì;* ẹni tó ń bá a gbé apata sì ń lọ níwájú rẹ̀. 8 Ó wá dúró, ó nahùn jáde sí ìlà ogun Ísírẹ́lì,+ ó sì sọ fún wọn pé: “Kí nìdí tí ẹ fi jáde wá lọ́wọ̀ọ̀wọ́ láti jagun? Ṣebí èmi ni alágbára Filísínì, ẹ̀yin sì ni ìránṣẹ́ Sọ́ọ̀lù. Torí náà, ẹ yan ọkùnrin kan lára yín kó wá bá mi. 9 Tó bá lè bá mi jà, tó sì mú mi balẹ̀, a ó di ìránṣẹ́ yín. Àmọ́ tí mo bá borí rẹ̀, tí mo sì mú un balẹ̀, ẹ ó di ìránṣẹ́ wa, ẹ ó sì máa sìn wá.” 10 Filísínì náà wá sọ pé: “Mo pẹ̀gàn ìlà ogun Ísírẹ́lì*+ lónìí yìí. Ẹ rán ọkùnrin kan sí mi, kí a jọ figẹ̀ wọngẹ̀!”
11 Ìgbà tí Sọ́ọ̀lù àti gbogbo Ísírẹ́lì gbọ́ ọ̀rọ̀ tí Filísínì náà sọ, àyà wọn já, ẹ̀rù sì bà wọ́n gan-an.
12 Dáfídì jẹ́ ọmọ Jésè ará Éfúrátà+ láti Bẹ́tílẹ́hẹ́mù+ ti Júdà. Jésè+ ní ọmọkùnrin mẹ́jọ,+ ó sì ti darúgbó gan-an ní ayé ìgbà Sọ́ọ̀lù. 13 Àwọn mẹ́ta tó dàgbà jù lára àwọn ọmọkùnrin Jésè ti tẹ̀ lé Sọ́ọ̀lù lọ sí ogun.+ Orúkọ àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta tó lọ sójú ogun ni Élíábù+ àkọ́bí, Ábínádábù+ ìkejì àti Ṣámà ìkẹta.+ 14 Dáfídì ló kéré jù,+ àwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta tó dàgbà jù sì tẹ̀ lé Sọ́ọ̀lù.
15 Nígbà tí Dáfídì wà lọ́dọ̀ Sọ́ọ̀lù, ó máa ń lọ sí Bẹ́tílẹ́hẹ́mù láti lọ tọ́jú àwọn àgùntàn+ bàbá rẹ̀, á sì pa dà. 16 Lákòókò yìí, ó ti pé ogójì (40) ọjọ́ tí Filísínì náà ti ń jáde wá tí á sì dúró láràárọ̀ àti ní ìrọ̀lẹ́-ìrọ̀lẹ́.
17 Ìgbà náà ni Jésè sọ fún Dáfídì ọmọ rẹ̀ pé: “Jọ̀wọ́, gba àyangbẹ ọkà òṣùwọ̀n eéfà* yìí àti búrẹ́dì mẹ́wàá yìí, kí o tètè gbé e lọ fún àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ ní ibùdó. 18 Gba wàrà* mẹ́wàá yìí lọ fún olórí ẹgbẹ̀rún; bákan náà, kí o wo àlàáfíà àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ, kí o sì gba àmì ìdánilójú bọ̀ látọ̀dọ̀ wọn.” 19 Wọ́n wà pẹ̀lú Sọ́ọ̀lù àti gbogbo àwọn ọkùnrin Ísírẹ́lì yòókù ní Àfonífojì* Élà,+ wọ́n ń bá àwọn Filísínì jà.+
20 Nítorí náà, Dáfídì dìde ní àárọ̀ kùtù, ó sì fi ẹnì kan ti àwọn àgùntàn; ó di ẹrù náà, ó sì lọ bí Jésè ti pàṣẹ fún un. Nígbà tí ó dé etí ibùdó, àwọn ọmọ ogun ń jáde lọ sí ìlà ogun, wọ́n sì ń kígbe ogun. 21 Ísírẹ́lì àti àwọn Filísínì tò lọ́wọ̀ọ̀wọ́ láti bẹ̀rẹ̀ ìjà, ìlà ogun kan sì dojú kọ ìlà ogun kejì. 22 Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, Dáfídì gbé ẹrù rẹ̀ ti ẹni tó ń bójú tó ẹrù, ó sì sáré lọ sí ìlà ogun. Nígbà tó dé ibẹ̀, ó bẹ̀rẹ̀ sí í béèrè àlàáfíà àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀.+
23 Bó ṣe ń bá wọn sọ̀rọ̀ lọ́wọ́, akọgun tó ń jẹ́ Gòláyátì+ dé, Filísínì tó wá láti Gátì. Ó jáde wá láti ìlà ogun àwọn Filísínì, ó tún sọ ọ̀rọ̀ tó máa ń sọ,+ Dáfídì sì gbọ́ ohun tó sọ. 24 Nígbà tí gbogbo ọkùnrin Ísírẹ́lì rí ọkùnrin náà, wọ́n sá sẹ́yìn, jìnnìjìnnì sì bá wọn.+ 25 Àwọn ọkùnrin Ísírẹ́lì ń sọ pé: “Ṣé ẹ rí ọkùnrin tó ń jáde bọ̀ yìí? Ńṣe ló wá pẹ̀gàn Ísírẹ́lì.*+ Ọrọ̀ tó pọ̀ ni ọba máa fún ọkùnrin tó bá mú un balẹ̀, á tún fún un ní ọmọbìnrin rẹ̀,+ ilé bàbá rẹ̀ kò sì ní san nǹkan kan mọ́ ní Ísírẹ́lì.”
26 Dáfídì béèrè lọ́wọ́ àwọn ọkùnrin tó dúró nítòsí rẹ̀ pé: “Kí ni wọ́n máa ṣe fún ọkùnrin tó bá mú Filísínì tó wà níbẹ̀ yẹn balẹ̀, tó sì mú ẹ̀gàn kúrò lórí Ísírẹ́lì? Ta tiẹ̀ ni Filísínì aláìdádọ̀dọ́* yìí tí á fi máa pẹ̀gàn ìlà ogun Ọlọ́run alààyè?”+ 27 Ni àwọn èèyàn náà bá sọ ohun tí wọ́n sọ tẹ́lẹ̀ fún un pé: “Ohun tí wọ́n máa ṣe fún ọkùnrin tó bá mú un balẹ̀ nìyí.” 28 Nígbà tí Élíábù+ ẹ̀gbọ́n rẹ̀ àgbà gbọ́ tó ń bá àwọn ọkùnrin náà sọ̀rọ̀, inú bí i gan-an sí Dáfídì, ó sọ pé: “Kí lo wá débí? Ta lo fi ìwọ̀nba àgùntàn yẹn tì ní aginjù?+ Mo mọ̀ dáadáa pé o máa ń kọjá àyè rẹ, mo sì mọ èrò burúkú tó wà lọ́kàn rẹ; torí kí o lè rí ohun tó ń ṣẹlẹ̀ lójú ogun lo ṣe wá.” 29 Ni Dáfídì bá fèsì pé: “Kí ni mo tún ṣe báyìí? Ṣebí mo kàn béèrè ọ̀rọ̀ ni!” 30 Torí náà, ó yíjú kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀ sí ẹlòmíì, ó sì béèrè ohun tó béèrè tẹ́lẹ̀,+ àwọn èèyàn náà sì fún un lésì bíi ti tẹ́lẹ̀.+
31 Ọ̀rọ̀ tí Dáfídì sọ ta sí àwọn kan létí, wọ́n sì lọ sọ fún Sọ́ọ̀lù. Torí náà, ó ránṣẹ́ pè é. 32 Dáfídì sọ fún Sọ́ọ̀lù pé: “Kí ọkàn ẹnikẹ́ni má ṣe domi* nítorí ọkùnrin náà. Ìránṣẹ́ rẹ máa lọ bá Filísínì náà jà.”+ 33 Ṣùgbọ́n Sọ́ọ̀lù sọ fún Dáfídì pé: “O ò lè lọ bá Filísínì yìí jà, torí ọmọdé ni ọ́,+ àmọ́ jagunjagun* ni òun láti ìgbà èwe rẹ̀.” 34 Ni Dáfídì bá sọ fún Sọ́ọ̀lù pé: “Nígbà tí ìránṣẹ́ rẹ ń ṣọ́ agbo ẹran bàbá rẹ̀, kìnnìún+ kan wá, lẹ́yìn náà bíárì kan wá pẹ̀lú, ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn sì gbé àgùntàn lọ nínú agbo ẹran. 35 Mo gbá tẹ̀ lé e, mo mú un balẹ̀, mo sì gba àgùntàn náà sílẹ̀ lẹ́nu rẹ̀. Nígbà tó dìde sí mi, mo gbá a mú níbi irun ọrùn rẹ̀,* mo mú un balẹ̀, mo sì pa á. 36 Àti kìnnìún àti bíárì náà ni ìránṣẹ́ rẹ pa, Filísínì aláìdádọ̀dọ́* yìí á sì dà bí ọ̀kan lára wọn, nítorí ó ti pẹ̀gàn àwọn ìlà ogun Ọlọ́run alààyè.”*+ 37 Dáfídì wá fi kún un pé: “Jèhófà tó gbà mí lọ́wọ́* kìnnìún àti bíárì náà, ló máa gbà mí lọ́wọ́ Filísínì yìí.”+ Sọ́ọ̀lù bá sọ fún Dáfídì pé: “Máa lọ, kí Jèhófà wà pẹ̀lú rẹ.”
38 Sọ́ọ̀lù wá gbé ẹ̀wù rẹ̀ wọ Dáfídì. Ó fi akoto* bàbà dé e lórí, lẹ́yìn náà ó gbé ẹ̀wù irin wọ̀ ọ́. 39 Dáfídì sì di idà rẹ̀ mọ́ ẹ̀wù rẹ̀, ó fẹ́ máa lọ, àmọ́ kò lè rìn, nítorí kò mọ́ ọn lára. Ni Dáfídì bá sọ fún Sọ́ọ̀lù pé: “Mi ò lè wọ nǹkan wọ̀nyí rìn, nítorí wọn ò mọ́ mi lára.” Torí náà, Dáfídì bọ́ wọn kúrò. 40 Ó mú ọ̀pá rẹ̀ dání, ó ṣa òkúta márùn-ún tó jọ̀lọ̀ nínú odò, ó kó wọn sínú àpò tí ó fi ń ṣe olùṣọ́ àgùntàn, kànnàkànnà+ rẹ̀ sì wà lọ́wọ́ rẹ̀. Ó sì ń bọ̀ lọ́dọ̀ Filísínì náà.
41 Filísínì náà ń sún mọ́ Dáfídì, ẹni tó ń bá a gbé apata rẹ̀ sì wà níwájú rẹ̀. 42 Nígbà tí Filísínì náà rí Dáfídì lọ́ọ̀ọ́kán, ó wò ó tẹ̀gàntẹ̀gàn torí pé ọmọdé ni, ó pupa, ó sì rẹwà.+ 43 Ni Filísínì náà bá sọ fún Dáfídì pé: “Ṣé ajá+ lo fi mí pè ni, tí o fi ń mú ọ̀pá bọ̀ wá bá mi jà?” Filísínì náà bá fi Dáfídì gégùn-ún ní orúkọ àwọn ọlọ́run rẹ̀. 44 Filísínì náà sọ fún Dáfídì pé: “Ṣáà máa bọ̀ lọ́dọ̀ mi, màá fi ẹran ara rẹ fún àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run àti àwọn ẹranko inú igbó.”
45 Dáfídì fún Filísínì náà lésì pé: “Ìwọ ń mú idà àti ọ̀kọ̀ àti ẹ̀ṣín*+ bọ̀ wá bá mi jà, ṣùgbọ́n èmi ń bọ̀ wá bá ọ ní orúkọ Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun,+ Ọlọ́run ìlà ogun Ísírẹ́lì, ẹni tí o pẹ̀gàn.*+ 46 Lónìí yìí, Jèhófà yóò fi ọ́ lé mi lọ́wọ́,+ màá mú ọ balẹ̀, màá sì gé orí rẹ kúrò. Lónìí yìí kan náà, màá fi òkú àwọn tó wà ní ibùdó àwọn Filísínì fún àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run àti àwọn ẹran inú igbó; gbogbo àwọn èèyàn tó wà láyé yóò sì mọ̀ pé Ọlọ́run kan wà ní Ísírẹ́lì.+ 47 Gbogbo àwọn tó pé jọ síbí* yóò mọ̀ pé kì í ṣe idà tàbí ọ̀kọ̀ ni Jèhófà fi ń gbani là,+ torí ogun náà jẹ́ ti Jèhófà,+ á sì fi gbogbo yín lé wa lọ́wọ́.”+
48 Ni Filísínì náà bá dìde, ó sì ń bọ̀ tààràtà láti pàdé Dáfídì, àmọ́ Dáfídì tètè sáré lọ sí ìlà ogun láti pàdé rẹ̀. 49 Dáfídì ki ọwọ́ bọ inú àpò rẹ̀, ó mú òkúta kan níbẹ̀, ó sì ta á. Ó ba iwájú orí Filísínì náà, òkúta náà wọ orí rẹ̀ lọ, ó sì ṣubú ní ìdojúbolẹ̀.+ 50 Bí Dáfídì ṣe fi kànnàkànnà àti òkúta kan ṣẹ́gun Filísínì náà nìyẹn; ó mú Filísínì náà balẹ̀, ó sì pa á, bó tilẹ̀ jẹ́ pe kò sí idà lọ́wọ́ Dáfídì.+ 51 Dáfídì sáré lọ, ó sì dúró ti Filísínì náà. Ó gbá idà Filísínì+ náà mú, ó fà á yọ nínú àkọ̀ rẹ̀, ó sì fi gé orí rẹ̀ kúrò kó lè rí i dájú pé ó ti kú. Nígbà tí àwọn Filísínì rí i pé alágbára wọn ti kú, wọ́n fẹsẹ̀ fẹ.+
52 Ni àwọn ọkùnrin Ísírẹ́lì àti ti Júdà bá dìde, wọ́n kígbe, wọ́n sì lépa àwọn Filísínì láti àfonífojì+ títí lọ dé àwọn ẹnubodè Ẹ́kírónì,+ àwọn Filísínì tó kú sì wà nílẹ̀ lójú ọ̀nà láti Ṣááráímù,+ títí dé Gátì àti Ẹ́kírónì. 53 Lẹ́yìn tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pa dà lẹ́yìn àwọn Filísínì tí wọ́n lé lọ kíkankíkan, wọ́n kó ẹrù tó wà ní ibùdó wọn.
54 Dáfídì gbé orí Filísínì náà wá sí Jerúsálẹ́mù, àmọ́ ó kó àwọn ohun ìjà Filísínì náà sínú àgọ́ tirẹ̀.+
55 Gbàrà tí Sọ́ọ̀lù rí Dáfídì tó ń jáde lọ pàdé Filísínì náà, ó bi Ábínérì+ olórí ọmọ ogun pé: “Ábínérì, ọmọ ta ni ọmọdékùnrin yìí?”+ Ábínérì fèsì pé: “Bí o* ti wà láàyè, ìwọ ọba, mi ò mọ̀!” 56 Ọba wá sọ pé: “Lọ wádìí ọmọ ẹni tí ọ̀dọ́kùnrin náà jẹ́.” 57 Torí náà, gbàrà tí Dáfídì pa dà láti ibi tó ti lọ pa Filísínì náà, Ábínérì mú un wá síwájú Sọ́ọ̀lù pẹ̀lú orí Filísínì+ náà ní ọwọ́ rẹ̀. 58 Sọ́ọ̀lù wá sọ fún un pé: “Ọmọ ta ni ọ́, ìwọ ọmọdékùnrin yìí?” Dáfídì fèsì pé: “Ọmọ Jésè + ìránṣẹ́ rẹ ará Bẹ́tílẹ́hẹ́mù ni.”+
18 Gbàrà tí Dáfídì bá Sọ́ọ̀lù sọ̀rọ̀ tán, Jónátánì+ àti Dáfídì wá di ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́,* Jónátánì sì bẹ̀rẹ̀ sí í nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ bí ara rẹ̀.*+ 2 Láti ọjọ́ yẹn lọ, Sọ́ọ̀lù mú Dáfídì sọ́dọ̀, kò sì jẹ́ kó pa dà sí ilé bàbá rẹ̀.+ 3 Jónátánì àti Dáfídì dá májẹ̀mú,+ torí pé ó nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ bí ara rẹ̀.*+ 4 Jónátánì bọ́ aṣọ àwọ̀lékè tí kò lápá tí ó wọ̀, ó sì fún Dáfídì, ó tún fún un ní ìbòrí rẹ̀, idà rẹ̀, ọrun rẹ̀ àti àmùrè rẹ̀ pẹ̀lú. 5 Dáfídì bẹ̀rẹ̀ sí í jáde lọ, ó sì ń ṣàṣeyọrí*+ níbikíbi tí Sọ́ọ̀lù bá rán an. Torí náà, Sọ́ọ̀lù ní kó máa bójú tó àwọn jagunjagun,+ èyí sì dùn mọ́ gbogbo àwọn èèyàn náà nínú àti àwọn ìránṣẹ́ Sọ́ọ̀lù pẹ̀lú.
6 Nígbà tí Dáfídì àti àwọn tó kù ń pa dà láti ibi tí wọ́n ti lọ pa àwọn Filísínì, àwọn obìnrin jáde látinú gbogbo ìlú Ísírẹ́lì láti fi orin+ àti ijó pàdé Ọba Sọ́ọ̀lù, wọ́n ń lu ìlù tanboríìnì,+ wọ́n sì ń ta gòjé tìdùnnútìdùnnú. 7 Àwọn obìnrin tó ń ṣe ayẹyẹ náà ń kọrin pé:
“Sọ́ọ̀lù ti pa ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọ̀tá,
Àmọ́ Dáfídì pa ẹgbẹẹgbàárùn-ún ọ̀tá.”+
8 Inú bí Sọ́ọ̀lù gan-an,+ orin yìí sì bà á lọ́kàn jẹ́, ó sọ pé: “Wọ́n fún Dáfídì ní ẹgbẹẹgbàárùn-ún, àmọ́ wọ́n fún mi ní ẹgbẹẹgbẹ̀rún. Ipò ọba nìkan ló kù kí wọ́n fún un!”+ 9 Láti ọjọ́ yẹn lọ, ìgbà gbogbo ni Sọ́ọ̀lù ń wo Dáfídì tìfuratìfura.
10 Lọ́jọ́ kejì, Ọlọ́run jẹ́ kí ẹ̀mí búburú mú Sọ́ọ̀lù,+ ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe wọ́nranwọ̀nran* nínú ilé, bí Dáfídì ṣe ń fi háàpù+ kọrin lọ́wọ́ bíi ti àtẹ̀yìnwá. Ọ̀kọ̀ kan wà lọ́wọ́ Sọ́ọ̀lù,+ 11 ó sì ju ọ̀kọ̀ náà,+ ó sọ fún ara rẹ̀ pé: ‘Màá gún Dáfídì mọ́ ògiri!’ Àmọ́ Dáfídì sá mọ́ ọn lọ́wọ́ lẹ́ẹ̀mejì. 12 Sọ́ọ̀lù wá ń bẹ̀rù Dáfídì torí pé Jèhófà wà pẹ̀lú rẹ̀,+ àmọ́ Ó ti fi Sọ́ọ̀lù sílẹ̀.+ 13 Torí náà, Sọ́ọ̀lù mú un kúrò níwájú rẹ̀, ó sì yàn án ṣe olórí ẹgbẹ̀rún, Dáfídì sì máa ń kó àwọn ọmọ ogun náà lọ sójú ogun.*+ 14 Dáfídì ń ṣàṣeyọrí*+ nínú gbogbo ohun tó ń ṣe, Jèhófà sì wà pẹ̀lú rẹ̀.+ 15 Bí Sọ́ọ̀lù ṣe rí i pé ó túbọ̀ ń ṣàṣeyọrí, ẹ̀rù rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í bà á. 16 Àmọ́ gbogbo Ísírẹ́lì àti Júdà nífẹ̀ẹ́ Dáfídì, nítorí pé òun ló ń kó wọn jáde.
17 Nígbà tó yá, Sọ́ọ̀lù sọ fún Dáfídì pé: “Wo Mérábù+ ọmọbìnrin mi àgbà. Màá fún ọ kí o fi ṣe aya.+ Síbẹ̀, jẹ́ kí n máa rí i pé o nígboyà, kí o sì máa ja àwọn ogun Jèhófà.”+ Torí Sọ́ọ̀lù sọ lọ́kàn ara rẹ̀ pé: ‘Mi ò ní fi ọwọ́ ara mi pa á. Àwọn Filísínì ló máa pa á.’+ 18 Ni Dáfídì bá sọ fún Sọ́ọ̀lù pé: “Ta ni mí, ta sì ni àwọn ẹbí mi àti ìdílé bàbá mi ní Ísírẹ́lì, tí màá fi di àna* ọba?”+ 19 Àmọ́, nígbà tí ó tó àkókò láti fún Dáfídì ní Mérábù ọmọ Sọ́ọ̀lù, wọ́n ti fi í fún Ádíríélì+ ará Méhólá láti fi ṣe aya.
20 Míkálì, ọmọbìnrin Sọ́ọ̀lù,+ nífẹ̀ẹ́ Dáfídì gan-an, wọ́n sọ fún Sọ́ọ̀lù nípa rẹ̀, inú rẹ̀ sì dùn sí i. 21 Torí náà, Sọ́ọ̀lù sọ pé: “Màá fi fún un kó lè di ìdẹkùn fún un, kí ọwọ́ àwọn Filísínì lè tẹ̀ ẹ́.”+ Sọ́ọ̀lù bá sọ fún Dáfídì lẹ́ẹ̀kejì pé: “Wàá di àna* mi lónìí yìí.” 22 Yàtọ̀ síyẹn, Sọ́ọ̀lù pàṣẹ fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pé: “Ẹ bá Dáfídì sọ̀rọ̀ ní bòókẹ́lẹ́ pé, ‘Wò ó! Inú ọba dùn sí ọ, gbogbo ìránṣẹ́ rẹ̀ sì gba tìẹ. Ní báyìí, bá ọba dána.’” 23 Nígbà tí àwọn ìránṣẹ́ Sọ́ọ̀lù sọ ọ̀rọ̀ wọ̀nyí fún Dáfídì, Dáfídì sọ pé: “Ṣé nǹkan kékeré ni lójú yín láti bá ọba dána, nígbà tí mo jẹ́ ọkùnrin aláìní àti ẹni tí a kò fi bẹ́ẹ̀ kà sí?”+ 24 Ìgbà náà ni àwọn ìránṣẹ́ Sọ́ọ̀lù ròyìn ohun tí Dáfídì sọ fún un.
25 Sọ́ọ̀lù wá sọ pé: “Ohun tí ẹ máa sọ fún Dáfídì nìyí, ‘Ọba ò fẹ́ nǹkan ìdána kankan,+ àfi ọgọ́rùn-ún (100) adọ̀dọ́+ àwọn Filísínì, kó lè gbẹ̀san lára àwọn ọ̀tá rẹ̀.’” Torí Sọ́ọ̀lù ń gbèrò pé kí Dáfídì ti ọwọ́ àwọn Filísínì ṣubú. 26 Torí náà, àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ sọ ọ̀rọ̀ náà fún Dáfídì, ó sì dára lójú Dáfídì láti bá ọba dána.+ Ṣáájú àkókò tí wọ́n dá, 27 Dáfídì àti àwọn ọkùnrin rẹ̀ lọ, wọ́n sì pa igba (200) lára àwọn ọkùnrin Filísínì, Dáfídì kó gbogbo adọ̀dọ́ wọn wá fún ọba, kó lè bá ọba dána. Torí náà, Sọ́ọ̀lù fún un ní Míkálì ọmọ rẹ̀ láti fi ṣe aya.+ 28 Sọ́ọ̀lù wá rí i pé Jèhófà wà pẹ̀lú Dáfídì+ àti pé Míkálì ọmọ rẹ̀ nífẹ̀ẹ́ Dáfídì.+ 29 Èyí mú kí Sọ́ọ̀lù túbọ̀ máa bẹ̀rù Dáfídì, Sọ́ọ̀lù sì wá di ọ̀tá Dáfídì jálẹ̀ ọjọ́ ayé rẹ̀.+
30 Àwọn ìjòyè Filísínì máa ń lọ sí ogun, àmọ́ ní gbogbo ìgbà tí wọ́n bá lọ, Dáfídì máa ń ṣàṣeyọrí* ju gbogbo àwọn ìránṣẹ́ Sọ́ọ̀lù;+ wọ́n sì wá gbé orúkọ rẹ̀ ga gan-an.+
19 Nígbà tó yá, Sọ́ọ̀lù bá Jónátánì ọmọ rẹ̀ àti gbogbo àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ sọ̀rọ̀ lórí bó ṣe máa pa Dáfídì.+ 2 Nítorí pé Jónátánì ọmọ Sọ́ọ̀lù nífẹ̀ẹ́ Dáfídì+ gan-an, ó sọ fún Dáfídì pé: “Sọ́ọ̀lù bàbá mi fẹ́ pa ọ́. Jọ̀wọ́ múra láàárọ̀ ọ̀la, sá lọ sí ibi ìkọ̀kọ̀ kan, kí o sì fara pa mọ́ síbẹ̀. 3 Màá jáde lọ, màá sì dúró lẹ́gbẹ̀ẹ́ bàbá mi nínú pápá tí o máa wà. Màá bá bàbá mi sọ̀rọ̀ nípa rẹ, tí mo bá sì gbọ́ ohunkóhun, màá rí i pé mo sọ fún ọ.”+
4 Torí náà, Jónátánì sọ̀rọ̀ Dáfídì ní rere+ níwájú Sọ́ọ̀lù bàbá rẹ̀. Ó sọ fún un pé: “Kí ọba má ṣàìdáa sí* Dáfídì ìránṣẹ́ rẹ̀, nítorí kò ṣẹ̀ ọ́, àwọn ohun tó ṣe fún ọ sì ti ṣe ọ́ láǹfààní. 5 Ó fi ẹ̀mí rẹ̀ wewu* kó lè pa Filísínì náà,+ tí Jèhófà sì mú kí gbogbo Ísírẹ́lì ṣẹ́gun* lọ́nà tó kàmàmà. O rí i, inú rẹ sì dùn gan-an. Kí ló wá dé tí o fẹ́ fi pa Dáfídì láìnídìí, tí wàá sì ní ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ lọ́rùn?”+ 6 Sọ́ọ̀lù fetí sí Jónátánì, Sọ́ọ̀lù sì búra pé: “Bí Jèhófà ti wà láàyè, a ò ní pa á.” 7 Lẹ́yìn náà, Jónátánì pe Dáfídì, ó sì sọ gbogbo nǹkan yìí fún un. Jónátánì wá mú Dáfídì wá sọ́dọ̀ Sọ́ọ̀lù, ó sì ń ṣe ìránṣẹ́ fún un bíi ti tẹ́lẹ̀.+
8 Nígbà tó yá, ogun tún bẹ́ sílẹ̀, Dáfídì sì jáde lọ bá àwọn Filísínì jà, ó pa wọ́n lọ rẹpẹtẹ, wọ́n sì sá kúrò níwájú rẹ̀.
9 Jèhófà jẹ́ kí ẹ̀mí búburú mú Sọ́ọ̀lù+ nígbà tó jókòó nínú ilé rẹ̀, tí ọ̀kọ̀ rẹ̀ sì wà lọ́wọ́ rẹ̀, bí Dáfídì ṣe ń fi háàpù+ kọrin lọ́wọ́. 10 Sọ́ọ̀lù fẹ́ fi ọ̀kọ̀ gún Dáfídì mọ́ ògiri, àmọ́ ó yẹ ọ̀kọ̀ Sọ́ọ̀lù, ọ̀kọ̀ náà sì wọnú ògiri. Dáfídì sì sá lọ ní òru ọjọ́ yẹn. 11 Lẹ́yìn náà, Sọ́ọ̀lù rán àwọn òjíṣẹ́ sí ilé Dáfídì láti máa ṣọ́ ọ, kí wọ́n sì pa á ní àárọ̀ ọjọ́ kejì,+ ṣùgbọ́n Míkálì ìyàwó Dáfídì sọ fún un pé: “Tí o kò bá sá lọ* ní òru òní, wọ́n á pa ọ́ kó tó dọ̀la.” 12 Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, Míkálì sọ Dáfídì kalẹ̀ gba ojú fèrèsé,* kí ó lè sá àsálà. 13 Míkálì mú ère tẹ́ráfímù,* ó tẹ́ ẹ sórí ibùsùn, ó sì fi àwọ̀n tó ní irun ewúrẹ́ sí ibi orí rẹ̀, lẹ́yìn náà ó fi aṣọ bò ó.
14 Sọ́ọ̀lù wá rán àwọn òjíṣẹ́ láti mú Dáfídì, àmọ́ Míkálì sọ pé: “Ara rẹ̀ ò yá.” 15 Torí náà, Sọ́ọ̀lù rán àwọn òjíṣẹ́ náà láti lọ rí Dáfídì, ó sì sọ pé: “Ẹ gbé e wá fún mi lórí ibùsùn rẹ̀, kí n lè pa á.”+ 16 Nígbà tí àwọn òjíṣẹ́ náà wọlé, ère tẹ́ráfímù* ló wà lórí ibùsùn náà, àwọ̀n tó ní irun ewúrẹ́ ló sì wà níbi tó yẹ kí orí rẹ̀ wà. 17 Sọ́ọ̀lù wá sọ fún Míkálì pé: “Kí ló dé tí o fi tàn mí báyìí, tí o sì jẹ́ kí ọ̀tá mi+ lọ kí ó lè sá àsálà?” Míkálì dá Sọ́ọ̀lù lóhùn pé: “Ó sọ fún mi pé, ‘Jẹ́ kí n lọ, bí bẹ́ẹ̀ kọ́, màá pa ọ́?’”
18 Dáfídì sá àsálà, ó sì sá lọ sọ́dọ̀ Sámúẹ́lì ní Rámà.+ Ó sọ gbogbo ohun tí Sọ́ọ̀lù ti ṣe sí i fún Sámúẹ́lì. Òun àti Sámúẹ́lì bá jáde lọ, wọ́n sì dúró sí Náótì.+ 19 Nígbà tó yá, wọ́n sọ fún Sọ́ọ̀lù pé: “Wò ó! Dáfídì wà ní Náótì ní Rámà.” 20 Ní kíá, Sọ́ọ̀lù rán àwọn òjíṣẹ́ láti lọ mú Dáfídì. Nígbà tí wọ́n rí àwọn tó dàgbà lára àwọn wòlíì tí wọ́n ń sọ tẹ́lẹ̀, tí Sámúẹ́lì sì dúró tó ń ṣe olórí wọn, ẹ̀mí Ọlọ́run bà lé àwọn òjíṣẹ́ Sọ́ọ̀lù, àwọn náà sì bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe bíi wòlíì.
21 Nígbà tí wọ́n sọ fún Sọ́ọ̀lù, lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, ó rán àwọn òjíṣẹ́ míì, àwọn náà sì bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe bíi wòlíì. Sọ́ọ̀lù bá tún rán àwọn òjíṣẹ́ lọ, àwùjọ kẹta, àwọn náà sì bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe bíi wòlíì. 22 Níkẹyìn, òun náà lọ sí Rámà. Nígbà tí ó dé kòtò omi ńlá tó wà ní Sékù, ó béèrè pé: “Ibo ni Sámúẹ́lì àti Dáfídì wà?” Wọ́n fèsì pé: “Wọ́n wà ní Náótì+ ní Rámà.” 23 Bí Sọ́ọ̀lù ṣe ń lọ láti ibẹ̀ sí Náótì ní Rámà, ẹ̀mí Ọlọ́run bà lé òun náà, Sọ́ọ̀lù sì ń bá wọn rìn lọ, ó ń ṣe bíi wòlíì títí ó fi dé Náótì ní Rámà. 24 Ó tún bọ́ aṣọ rẹ̀, òun náà sì ń ṣe bíi wòlíì níwájú Sámúẹ́lì, ó sùn sílẹ̀ ní ìhòòhò* ní gbogbo ọjọ́ yẹn àti ní gbogbo òru yẹn. Ìdí nìyẹn tí wọ́n fi ń sọ pé: “Ṣé Sọ́ọ̀lù náà wà lára àwọn wòlíì ni?”+
20 Nígbà náà, Dáfídì sá kúrò ní Náótì ní Rámà. Àmọ́, ó wá sọ́dọ̀ Jónátánì, ó ní: “Kí ni mo ṣe?+ Ọ̀ràn wo ni mo dá, ẹ̀ṣẹ̀ wo ni mo sì ṣẹ bàbá rẹ tí ó fi ń wá ẹ̀mí* mi?” 2 Ni Jónátánì bá sọ fún un pé: “Kò ṣeé gbọ́ sétí!+ O ò ní kú. Wò ó! Bàbá mi ò ní ṣe ohunkóhun, ì báà jẹ́ kékeré tàbí ńlá láìsọ fún mi. Báwo ni bàbá mi á ṣe fi irú ọ̀rọ̀ yìí pa mọ́ fún mi? Kò jẹ́ jẹ́ bẹ́ẹ̀.” 3 Ṣùgbọ́n Dáfídì fi kún un pé: “Bàbá rẹ mọ̀ dájú pé mo ti rí ojú rere rẹ,+ á sì sọ pé, ‘Ẹ má ṣe jẹ́ kí Jónátánì mọ̀, tó bá mọ̀, inú rẹ̀ á bà jẹ́.’ Àmọ́, bí Jèhófà ti wà láàyè, tí ìwọ náà* sì wà láàyè, ìṣísẹ̀ kan péré ló wà láàárín èmi àti ikú!”+
4 Ni Jónátánì bá sọ fún Dáfídì pé: “Ohunkóhun tí o* bá sọ ni màá ṣe fún ọ.” 5 Dáfídì wá sọ fún Jónátánì pé: “Ọ̀la ni òṣùpá tuntun,+ wọ́n á sì máa retí pé kí n jókòó pẹ̀lú ọba láti jẹun. Ní báyìí, jẹ́ kí n lọ fara pa mọ́ sínú pápá títí di ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ kẹta. 6 Tí bàbá rẹ bá ṣàárò mi, kí o sọ fún un pé, ‘Dáfídì tọrọ àyè lọ́wọ́ mi pé òun fẹ́ sáré lọ sí Bẹ́tílẹ́hẹ́mù+ ìlú òun, torí pé ẹbọ ọdọọdún kan wà tí gbogbo ìdílé+ rẹ̀ máa rú níbẹ̀.’ 7 Bí ó bá sọ pé, ‘Ó dára!’ á jẹ́ pé àlàáfíà wà fún ìránṣẹ́ rẹ. Ṣùgbọ́n bí ó bá bínú, kí o yáa mọ̀ pé ó ti pinnu láti ṣe mí ní jàǹbá. 8 Fi ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ hàn sí ìránṣẹ́ rẹ,+ nítorí o ti bá ìránṣẹ́ rẹ dá májẹ̀mú níwájú Jèhófà.+ Àmọ́ tí mo bá jẹ̀bi,+ ìwọ fúnra rẹ ni kí o pa mí. Má wulẹ̀ fà mí lé bàbá rẹ lọ́wọ́.”
9 Jónátánì fèsì pé: “Má tiẹ̀ jẹ́ kí irú èrò bẹ́ẹ̀ wá sí ọ lọ́kàn! Tí mo bá gbọ́ pé bàbá mi fẹ́ ṣe ọ́ ní jàǹbá, ṣé mi ò ní sọ fún ọ ni?”+ 10 Dáfídì bá sọ fún Jónátánì pé: “Ta ló máa wá sọ fún mi bóyá ohùn líle ni bàbá rẹ fi dá ọ lóhùn?” 11 Jónátánì sọ fún Dáfídì pé: “Wá, jẹ́ ká lọ sínú pápá.” Torí náà, àwọn méjèèjì jáde lọ sí pápá. 12 Jónátánì sì sọ fún Dáfídì pé: “Kí Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì ṣe ẹlẹ́rìí pé màá bi bàbá mi léèrè ọ̀rọ̀ ní ìwòyí ọ̀la, tàbí ní ọ̀túnla. Tí inú rẹ̀ bá yọ́ sí Dáfídì, màá ránṣẹ́ sí ọ, màá sì jẹ́ kí o mọ ohun tó bá sọ. 13 Àmọ́ tí bàbá mi bá ń gbèrò láti ṣe ọ́ ní jàǹbá, kí Jèhófà fìyà jẹ èmi Jónátánì gan-an, tí mi ò bá sọ fún ọ, kí n sì jẹ́ kí o lọ ní àlàáfíà. Kí Jèhófà wà pẹ̀lú rẹ,+ bí ó ṣe wà pẹ̀lú bàbá mi tẹ́lẹ̀.+ 14 Àbí, ṣé o ò ní fi ìfẹ́ Jèhófà tí kì í yẹ̀ hàn sí mi nígbà tí mo ṣì wà láàyè àti nígbà tí mo bá kú?+ 15 Má ṣe dáwọ́ ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ tí o ní sí agbo ilé mi dúró,+ kódà nígbà tí Jèhófà bá gbá gbogbo àwọn ọ̀tá Dáfídì kúrò lórí ilẹ̀.” 16 Torí náà, Jónátánì bá ilé Dáfídì dá májẹ̀mú, ó ní, “Jèhófà yóò béèrè, yóò sì pe àwọn ọ̀tá Dáfídì wá jíhìn.” 17 Torí náà, Jónátánì ní kí Dáfídì tún búra nítorí ìfẹ́ tí ó ní sí i, nítorí pé ó nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ bí ó ṣe nífẹ̀ẹ́ ara* rẹ̀.+
18 Jónátánì wá sọ fún un pé: “Ọ̀la ni òṣùpá tuntun,+ àárò rẹ á sọ wá, torí pé ìjókòó rẹ máa ṣófo. 19 Tó bá fi máa di ọjọ́ kẹta, àárò rẹ á ti máa sọ wá gan-an, kí o wá sí ibi tí o fara pa mọ́ sí lọ́jọ́sí,* kí o sì dúró sí tòsí òkúta tó wà níbí yìí. 20 Màá wá ta ọfà mẹ́ta sí apá ibì kan lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀, bíi pé nǹkan kan wà tí mo fẹ́ ta ọfà sí. 21 Nígbà tí mo bá rán ìránṣẹ́ mi, màá sọ fún un pé, ‘Lọ wá àwọn ọfà náà.’ Tí mo bá sọ fún ìránṣẹ́ náà pé, ‘Wò ó! Àwọn ọfà náà nìyẹn lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ, kó wọn,’ nígbà náà, bí Jèhófà ti wà láàyè, o lè pa dà wá torí pé ó túmọ̀ sí àlàáfíà fún ọ, kò sì séwu. 22 Ṣùgbọ́n tí mo bá sọ fún ọmọkùnrin náà pé, ‘Wò ó! Àwọn ọfà náà ṣì wà níwájú,’ nígbà náà, kí o máa lọ, nítorí pé Jèhófà fẹ́ kí o lọ. 23 Ní ti ìlérí tí èmi àti ìwọ jọ ṣe,+ kí Jèhófà wà láàárín wa títí láé.”+
24 Torí náà, Dáfídì fara pa mọ́ sí pápá. Nígbà tí òṣùpá tuntun yọ, ọba jókòó sí àyè rẹ̀ nídìí oúnjẹ láti jẹun.+ 25 Ọba jókòó síbi tó máa ń jókòó sí lẹ́gbẹ̀ẹ́ ògiri. Jónátánì dojú kọ ọ́, Ábínérì+ sì jókòó sẹ́gbẹ̀ẹ́ Sọ́ọ̀lù, àmọ́ àyè Dáfídì ṣófo. 26 Sọ́ọ̀lù kò sọ ohunkóhun lọ́jọ́ yẹn, torí ó sọ fún ara rẹ̀ pé: ‘Nǹkan kan ti ṣẹlẹ̀ tó sọ ọ́ di aláìmọ́.+ Ó dájú pé kò mọ́ ni.’ 27 Ní ọjọ́ tó tẹ̀ lé òṣùpá tuntun, ìyẹn lọ́jọ́ kejì, àyè Dáfídì ṣì ṣófo. Ni Sọ́ọ̀lù bá sọ fún Jónátánì ọmọ rẹ̀ pé: “Kí ló dé tí ọmọ Jésè+ kò fi wá síbi oúnjẹ lánàá àti lónìí?” 28 Jónátánì dá Sọ́ọ̀lù lóhùn pé: “Dáfídì tọrọ àyè lọ́wọ́ mi pé òun fẹ́ lọ sí Bẹ́tílẹ́hẹ́mù.+ 29 Ó sọ pé, ‘Jọ̀wọ́, jẹ́ kí n lọ, torí pé a ní ẹbọ ìdílé tí a fẹ́ rú ní ìlú náà, ẹ̀gbọ́n mi ló sì pè mí. Nítorí náà, tí mo bá rí ojú rere rẹ, jọ̀wọ́ jẹ́ kí n sáré lọ rí àwọn ẹ̀gbọ́n mi.’ Ìdí nìyẹn tí kò fi wá síbi tábìlì ọba.” 30 Nígbà náà, Sọ́ọ̀lù bínú gan-an sí Jónátánì, ó sì sọ fún un pé: “Ìwọ ọmọ ọlọ̀tẹ̀ obìnrin, ṣé o rò pé mi ò mọ̀ pé ò ń gbè sẹ́yìn ọmọ Jésè ni, tó sì máa já sí ìtìjú fún ìwọ àti ìyá rẹ?* 31 Ní gbogbo ìgbà tí ọmọ Jésè bá fi wà láàyè lórí ilẹ̀, ìwọ àti ipò ọba rẹ kò ní lè fìdí múlẹ̀.+ Ní báyìí, ní kí wọ́n lọ mú un wá fún mi, nítorí pé ó gbọ́dọ̀ kú.”*+
32 Àmọ́, Jónátánì sọ fún Sọ́ọ̀lù bàbá rẹ̀ pé: “Kí nìdí tí wọ́n á fi pa á?+ Kí ló ṣe?” 33 Ni Sọ́ọ̀lù bá ju ọ̀kọ̀ sí i láti fi gún un,+ Jónátánì sì wá mọ̀ pé bàbá òun ti pinnu láti pa Dáfídì.+ 34 Lójú ẹsẹ̀, Jónátánì bínú dìde kúrò nídìí tábìlì náà, kò sì jẹ oúnjẹ kankan ní ọjọ́ kejì lẹ́yìn òṣùpá tuntun, torí inú rẹ̀ bà jẹ́ nítorí Dáfídì+ àti pé bàbá rẹ̀ ti fi àbùkù kàn án.
35 Nígbà tó di àárọ̀, Jónátánì jáde lọ sí pápá nítorí àdéhùn òun àti Dáfídì, ìránṣẹ́ kan tó jẹ́ ọ̀dọ́ sì wà pẹ̀lú rẹ̀.+ 36 Ó wá sọ fún ìránṣẹ́ rẹ̀ pé: “Jọ̀wọ́, sáré lọ wá àwọn ọfà tí mo bá ta.” Ìránṣẹ́ náà bá sáré, Jónátánì sì ta ọfà náà kọjá rẹ̀. 37 Nígbà tí ìránṣẹ́ náà dé ibi tí Jónátánì ta ọfà náà sí, Jónátánì pe ìránṣẹ́ náà, ó ní: “Ọfà náà ṣì wà níwájú!” 38 Jónátánì bá pe ìránṣẹ́ náà pé: “Tètè lọ! Ṣe kíá! Má ṣe jáfara!” Ìránṣẹ́ Jónátánì ṣa àwọn ọfà náà, ó sì pa dà sọ́dọ̀ ọ̀gá rẹ̀. 39 Ìránṣẹ́ náà kò mọ ohun tó ń ṣẹlẹ̀; Jónátánì àti Dáfídì nìkan ló mọ ohun tó túmọ̀ sí. 40 Lẹ́yìn náà, Jónátánì kó àwọn ohun ìjà rẹ̀ fún ìránṣẹ́ rẹ̀, ó sì sọ fún un pé: “Gbà, kó wọn lọ sínú ìlú.”
41 Nígbà tí ìránṣẹ́ náà lọ, Dáfídì dìde láti ibì kan tó wà nítòsí lápá gúúsù. Ó wá kúnlẹ̀, ó sì tẹrí ba mọ́lẹ̀ nígbà mẹ́ta, wọ́n fi ẹnu ko ara wọn lẹ́nu, wọ́n sì sunkún fún ara wọn, àmọ́ Dáfídì ló sunkún jù. 42 Jónátánì sọ fún Dáfídì pé: “Máa lọ ní àlàáfíà, nítorí àwa méjèèjì ti fi orúkọ Jèhófà búra+ pé, ‘Kí Jèhófà wà láàárín èmi àti ìwọ àti láàárín àwọn ọmọ* mi àti àwọn ọmọ* rẹ títí láé.’”+
Dáfídì bá dìde, ó sì lọ, Jónátánì wá pa dà sínú ìlú.
21 Nígbà tó yá, Dáfídì wá sọ́dọ̀ àlùfáà Áhímélékì ní Nóbù.+ Jìnnìjìnnì bá Áhímélékì nígbà tó pàdé Dáfídì, ó sì sọ fún un pé: “Kí ló dé tí o fi dá wá, tí kò sẹ́ni tó tẹ̀ lé ọ?”+ 2 Dáfídì dá àlùfáà Áhímélékì lóhùn pé: “Ọba ní kí n ṣe ohun kan, àmọ́ ó sọ pé, ‘Má ṣe jẹ́ kí ẹnì kankan mọ ohunkóhun nípa iṣẹ́ tí mo rán ọ àti àṣẹ tí mo pa fún ọ.’ Torí náà, mo bá àwọn ọ̀dọ́kùnrin mi ṣe àdéhùn pé ká pàdé níbì kan. 3 Ní báyìí, tí búrẹ́dì márùn-ún bá wà ní ìkáwọ́ rẹ, ṣáà fún mi tàbí ohunkóhun tó bá wà.” 4 Àmọ́ àlùfáà náà dá Dáfídì lóhùn pé: “Kò sí búrẹ́dì lásán, búrẹ́dì mímọ́+ ló wà, tí àwọn ọ̀dọ́kùnrin náà kò bá ti fọwọ́ kan obìnrin.”*+ 5 Dáfídì dá àlùfáà náà lóhùn pé: “A ti rí i dájú pé a yẹra fún àwọn obìnrin bí a ti máa ń ṣe nígbà tí mo bá jáde ogun.+ Tí ara àwọn ọkùnrin náà bá wà ní mímọ́ nígbà tó jẹ́ pé iṣẹ́ tí kò fi bẹ́ẹ̀ ṣe pàtàkì ni wọ́n bá lọ, ṣé wọn ò ní wà ní mímọ́ nígbà tí wọ́n fẹ́ ṣiṣẹ́ pàtàkì bíi tòní yìí?” 6 Àlùfáà náà bá fún un ní búrẹ́dì mímọ́,+ torí pé kò sí búrẹ́dì míì nílẹ̀ àfi búrẹ́dì àfihàn, tí a mú kúrò níwájú Jèhófà kí a lè fi búrẹ́dì tuntun rọ́pò rẹ̀ ní ọjọ́ tí a mú un kúrò.
7 Ọ̀kan lára àwọn ìránṣẹ́ Sọ́ọ̀lù wà níbẹ̀ lọ́jọ́ yẹn, tí a dá dúró níwájú Jèhófà. Dóẹ́gì+ ni orúkọ rẹ̀, ará Édómù+ ni, òun sì ni olórí àwọn olùṣọ́ àgùntàn Sọ́ọ̀lù.
8 Dáfídì wá sọ fún Áhímélékì pé: “Ṣé ọ̀kọ̀ tàbí idà kankan wà ní ìkáwọ́ rẹ níbí? Mi ò mú idà mi tàbí àwọn ohun ìjà mi dání, nítorí iṣẹ́ ọba jẹ́ kánjúkánjú.” 9 Àlùfáà náà bá sọ pé: “Idà Gòláyátì+ ará Filísínì tí o pa ní Àfonífojì* Élà+ wà níbí, òun ni wọ́n faṣọ wé lẹ́yìn éfódì+ yẹn. Tí o bá fẹ́ mú un, o lè mú un, torí òun nìkan ló wà níbí.” Dáfídì wá sọ pé: “Kò sí èyí tó dà bíi rẹ̀. Mú un fún mi.”
10 Lọ́jọ́ yẹn, Dáfídì gbéra, ó tún bẹ̀rẹ̀ sí í sá lọ+ nítorí Sọ́ọ̀lù, níkẹyìn ó dé ọ̀dọ̀ Ákíṣì ọba Gátì.+ 11 Àwọn ìránṣẹ́ Ákíṣì sọ fún un pé: “Ṣé kì í ṣe Dáfídì ọba ilẹ̀ náà nìyí? Ṣé òun kọ́ ni wọ́n kọrin fún, tí wọ́n ń jó tí wọ́n sì ń sọ pé,
‘Sọ́ọ̀lù ti pa ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọ̀tá,
Àmọ́ Dáfídì pa ẹgbẹẹgbàárùn-ún ọ̀tá’?”+
12 Dáfídì fi ọ̀rọ̀ wọ̀nyí sọ́kàn, ẹ̀rù sì bẹ̀rẹ̀ sí í bà á gan-an+ nítorí Ákíṣì ọba Gátì. 13 Torí náà, ó díbọ́n lójú wọn bíi pé orí òun ti yí,+ ó sì ń ṣe bí ayírí láàárín wọn.* Ó ń ha ara àwọn ilẹ̀kùn ẹnubodè, ó sì ń wa itọ́ sí irùngbọ̀n rẹ̀. 14 Níkẹyìn, Ákíṣì sọ fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pé: “Ẹ rí i pé orí ọkùnrin yìí ti yí! Kí ló dé tí ẹ fi mú un wá sọ́dọ̀ mi? 15 Ṣé àwọn wèrè tó wà níbí kò tó ni, tí màá fi ní kí eléyìí wá máa ṣe wèrè níwájú mi? Ṣé ó yẹ kí irú ọkùnrin yìí wọ ilé mi?”
22 Nítorí náà, Dáfídì kúrò níbẹ̀,+ ó sì sá lọ sí ihò Ádúlámù.+ Nígbà tí àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀ àti gbogbo ilé bàbá rẹ̀ gbọ́, wọ́n lọ bá a níbẹ̀. 2 Gbogbo àwọn tó wà nínú wàhálà, àwọn tó jẹ gbèsè àti àwọn tó ní ẹ̀dùn ọkàn* kóra jọ sọ́dọ̀ rẹ̀, ó sì di olórí wọn. Nǹkan bí ọgọ́rùn-ún mẹ́rin (400) ọkùnrin ló wà pẹ̀lú rẹ̀.
3 Lẹ́yìn náà, Dáfídì fi ibẹ̀ sílẹ̀ lọ sí Mísípè ní Móábù, ó sì sọ fún ọba Móábù+ pé: “Jọ̀wọ́, jẹ́ kí bàbá mi àti ìyá mi máa gbé lọ́dọ̀ yín títí màá fi mọ ohun tí Ọlọ́run máa ṣe fún mi.” 4 Torí náà, ó fi wọ́n sọ́dọ̀ ọba Móábù, wọ́n sì ń gbé lọ́dọ̀ rẹ̀ ní gbogbo ìgbà tí Dáfídì fi wà ní ibi ààbò.+
5 Nígbà tó yá, wòlíì Gádì+ sọ fún Dáfídì pé: “Má ṣe gbé ní ibi ààbò mọ́. Lọ sí ilẹ̀ Júdà.”+ Torí náà, Dáfídì kúrò níbẹ̀, ó sì lọ sí igbó Hérétì.
6 Sọ́ọ̀lù gbọ́ pé wọ́n ti rí Dáfídì àti àwọn ọkùnrin tó wà pẹ̀lú rẹ̀. Sọ́ọ̀lù wà ní Gíbíà,+ ó jókòó sábẹ́ igi támáríkì ní ibi gíga, ọ̀kọ̀ rẹ̀ wà lọ́wọ́ rẹ̀, gbogbo àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ sì dúró yí i ká. 7 Ìgbà náà ni Sọ́ọ̀lù sọ fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ tó dúró yí i ká pé: “Ẹ jọ̀wọ́, ẹ fetí sílẹ̀, ẹ̀yin ọmọ Bẹ́ńjámínì. Ṣé ọmọ Jésè+ náà máa lè fún gbogbo yín ní ilẹ̀ àti ọgbà àjàrà? Ṣé ó máa fi gbogbo yín ṣe olórí ẹgbẹẹgbẹ̀rún àti olórí ọgọ́rọ̀ọ̀rún?+ 8 Gbogbo yín ti dìtẹ̀ sí mi! Kò sẹ́ni tó sọ fún mi nígbà tí ọmọ tèmi lọ bá ọmọ Jésè dá májẹ̀mú!+ Kò sí ìkankan nínú yín tó ṣàánú mi, tó sì sọ fún mi pé ọmọ mi rán ìránṣẹ́ mi pé kó lúgọ dè mí, bí ọ̀ràn ṣe rí yìí.”
9 Ìgbà náà ni Dóẹ́gì+ ọmọ Édómù tó ń bójú tó àwọn ìránṣẹ́ Sọ́ọ̀lù fèsì pé:+ “Mo rí ọmọ Jésè tó wá sí Nóbù lọ́dọ̀ Áhímélékì ọmọ Áhítúbù.+ 10 Ó bá a wádìí lọ́dọ̀ Jèhófà, ó sì fún un ní oúnjẹ. Ó tiẹ̀ tún fún un ní idà Gòláyátì ará Filísínì.”+ 11 Ní kíá, ọba ránṣẹ́ pe àlùfáà Áhímélékì ọmọ Áhítúbù àti gbogbo àlùfáà ilé baba rẹ̀ tó wà ní Nóbù. Torí náà, gbogbo wọn wá sọ́dọ̀ ọba.
12 Sọ́ọ̀lù wá sọ pé: “Jọ̀wọ́, fetí sílẹ̀, ìwọ ọmọ Áhítúbù!” Ó sì fèsì pé: “Èmi nìyí, olúwa mi.” 13 Sọ́ọ̀lù sọ fún un pé: “Kí nìdí tí o fi dìtẹ̀ sí mi, ìwọ àti ọmọ Jésè, tí o fún un ní búrẹ́dì àti idà, tí o sì bá a wádìí lọ́dọ̀ Ọlọ́run? Dáfídì ń ta kò mí, ó sì ń lúgọ dè mí, bí ọ̀ràn ṣe rí yìí.” 14 Áhímélékì bá dá ọba lóhùn pé: “Ta ló ṣeé fọkàn tán* láàárín àwọn ìránṣẹ́ ọba bíi Dáfídì?+ Àna ọba ni,+ ó jẹ́ olórí ẹ̀ṣọ́ rẹ, ẹni iyì sì ni nínú ilé rẹ.+ 15 Ṣé òní ni màá kọ́kọ́ bá a wádìí lọ́dọ̀ Ọlọ́run ni?+ Ohun tí ò ń sọ yìí kò wá sí mi lọ́kàn rí! Kí ọba má ṣe ka ohunkóhun sí ìránṣẹ́ rẹ̀ lọ́rùn àti sí gbogbo ilé baba mi, nítorí ìránṣẹ́ rẹ kò mọ nǹkan kan nípa ọ̀ràn náà.”+
16 Ṣùgbọ́n ọba sọ pé: “Áhímélékì, ó dájú pé wàá kú,+ ìwọ àti gbogbo ilé baba rẹ.”+ 17 Ni ọba bá sọ fún àwọn ẹ̀ṣọ́* tó dúró yí i ká pé: “Ẹ lọ pa àwọn àlùfáà Jèhófà, torí wọ́n ti gbè sẹ́yìn Dáfídì! Wọ́n mọ̀ pé ńṣe ló sá, wọn ò sì sọ fún mi!” Ṣùgbọ́n àwọn ìránṣẹ́ ọba kò fẹ́ gbé ọwọ́ wọn sókè láti pa àwọn àlùfáà Jèhófà. 18 Ìgbà náà ni ọba sọ fún Dóẹ́gì+ pé: “Ìwọ, lọ pa àwọn àlùfáà náà!” Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, Dóẹ́gì ọmọ Édómù+ lọ pa àwọn àlùfáà náà fúnra rẹ̀. Ọkùnrin márùnlélọ́gọ́rin (85) tó ń wọ éfódì+ tí a fi aṣọ ọ̀gbọ̀* ṣe ni ó pa lọ́jọ́ yẹn. 19 Ó tún fi idà ṣá àwọn ará Nóbù+ tó jẹ́ ìlú àwọn àlùfáà balẹ̀; ó pa ọkùnrin àti obìnrin, ọmọdé àti ọmọ jòjòló, akọ màlúù, kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ àti àgùntàn, gbogbo wọn ni ó fi idà pa.
20 Àmọ́ ṣá, ọ̀kan lára àwọn ọmọ Áhímélékì ọmọ Áhítúbù, tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Ábíátárì+ sá àsálà, ó sì lọ bá Dáfídì. 21 Ábíátárì sọ fún Dáfídì pé: “Sọ́ọ̀lù ti pa àwọn àlùfáà Jèhófà.” 22 Ni Dáfídì bá sọ fún Ábíátárì pé: “Mo mọ̀ lọ́jọ́ yẹn,+ tí Dóẹ́gì ọmọ Édómù wà níbẹ̀, pé kò ní ṣaláì sọ fún Sọ́ọ̀lù. Tìtorí mi ni wọ́n ṣe pa gbogbo àwọn* ará ilé baba rẹ. 23 Dúró sọ́dọ̀ mi. Má bẹ̀rù, torí ẹni tí ó bá ń wá ẹ̀mí* rẹ ń wá ẹ̀mí* mi; abẹ́ ààbò mi lo wà.”+
23 Nígbà tó yá, wọ́n sọ fún Dáfídì pé: “Àwọn Filísínì ń bá Kéílà+ jà, wọ́n sì ń kó wọn lẹ́rù ní àwọn ibi ìpakà.” 2 Torí náà, Dáfídì wádìí lọ́dọ̀ Jèhófà pé:+ “Ṣé kí n lọ mú àwọn Filísínì yìí balẹ̀?” Jèhófà sọ fún Dáfídì pé: “Lọ mú àwọn Filísínì náà balẹ̀, kí o sì gba Kéílà sílẹ̀.” 3 Àmọ́ àwọn ọkùnrin Dáfídì sọ fún un pé: “Wò ó! Bí a ṣe wà níbí ní Júdà,+ ẹ̀rù ṣì ń bà wá, ká má ṣẹ̀ṣẹ̀ wá sọ pé ká lọ sí Kéílà láti dojú kọ ìlà ogun àwọn Filísínì!”+ 4 Torí náà, Dáfídì wádìí lẹ́ẹ̀kan sí i lọ́dọ̀ Jèhófà.+ Jèhófà sì dá a lóhùn pé: “Dìde; lọ sí Kéílà torí màá fi àwọn Filísínì náà lé ọ lọ́wọ́.”+ 5 Dáfídì àti àwọn ọkùnrin rẹ̀ bá lọ sí Kéílà, ó sì bá àwọn Filísínì jà; ó kó àwọn ẹran ọ̀sìn wọn lọ, ó pa wọ́n lọ rẹpẹtẹ, Dáfídì sì gba àwọn tó ń gbé ní Kéílà+ sílẹ̀.
6 Nígbà tí Ábíátárì+ ọmọ Áhímélékì sá lọ sọ́dọ̀ Dáfídì ní Kéílà, éfódì kan wà lọ́wọ́ rẹ̀. 7 Wọ́n sọ fún Sọ́ọ̀lù pé: “Dáfídì ti wá sí Kéílà.” Sọ́ọ̀lù wá sọ pé: “Ọlọ́run ti fi í lé mi lọ́wọ́,*+ nítorí ó ti há ara rẹ̀ mọ́ bó ṣe wá sínú ìlú tó ní àwọn ilẹ̀kùn àti ọ̀pá ìdábùú.” 8 Nítorí náà, Sọ́ọ̀lù pe gbogbo àwọn èèyàn náà sí ogun, láti lọ sí Kéílà, kí wọ́n sì dó ti Dáfídì àti àwọn ọkùnrin rẹ̀. 9 Nígbà tí Dáfídì gbọ́ pé Sọ́ọ̀lù ń gbìmọ̀ ibi sí òun, ó sọ fún àlùfáà Ábíátárì pé: “Mú éfódì wá.”+ 10 Dáfídì wá sọ pé: “Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì, ìránṣẹ́ rẹ ti gbọ́ pé Sọ́ọ̀lù fẹ́ wá sí Kéílà láti pa ìlú náà run nítorí mi.+ 11 Ṣé àwọn olórí* Kéílà máa fi mí lé e lọ́wọ́? Ṣé Sọ́ọ̀lù máa wá lóòótọ́ bí ìránṣẹ́ rẹ ṣe gbọ́? Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì, jọ̀wọ́ sọ fún ìránṣẹ́ rẹ.” Ni Jèhófà bá fèsì pé: “Ó máa wá.” 12 Dáfídì béèrè pé: “Ṣé àwọn olórí Kéílà máa fi èmi àti àwọn ọkùnrin mi lé Sọ́ọ̀lù lọ́wọ́?” Jèhófà dáhùn pé: “Wọ́n á fi yín lé e lọ́wọ́.”
13 Ní kíá, Dáfídì àti àwọn ọkùnrin rẹ̀ dìde, nǹkan bí ọgọ́rùn-ún mẹ́fà (600) ni wọ́n,+ wọ́n kúrò ní Kéílà, wọ́n sì ń lọ sí ibikíbi tí wọ́n bá lè lọ. Nígbà tí Sọ́ọ̀lù gbọ́ pé Dáfídì ti sá kúrò ní Kéílà, kò wá a lọ mọ́. 14 Dáfídì ń gbé ní aginjù ní àwọn ibi tó ṣòroó dé, ní agbègbè olókè tó wà ní aginjù Sífù.+ Gbogbo ìgbà ni Sọ́ọ̀lù ń wá a kiri,+ àmọ́ Jèhófà kò fi lé e lọ́wọ́. 15 Dáfídì mọ̀ pé* Sọ́ọ̀lù ti jáde lọ láti gba ẹ̀mí* òun nígbà tí Dáfídì ṣì wà ní aginjù Sífù ní Hóréṣì.
16 Ni Jónátánì ọmọ Sọ́ọ̀lù bá lọ sọ́dọ̀ Dáfídì ní Hóréṣì, ó sì ràn án lọ́wọ́ kí ó lè túbọ̀ gbẹ́kẹ̀ lé* Jèhófà.+ 17 Ó sọ fún un pé: “Má bẹ̀rù, torí pé Sọ́ọ̀lù bàbá mi kò ní rí ọ mú; ìwọ lo máa di ọba Ísírẹ́lì,+ èmi ni màá di igbá kejì rẹ; Sọ́ọ̀lù bàbá mi náà sì mọ̀ bẹ́ẹ̀.”+ 18 Àwọn méjèèjì wá dá májẹ̀mú+ níwájú Jèhófà, Dáfídì dúró sí Hóréṣì, Jónátánì sì gba ilé rẹ̀ lọ.
19 Lẹ́yìn náà, àwọn ọkùnrin Sífù lọ sọ́dọ̀ Sọ́ọ̀lù ní Gíbíà,+ wọ́n sọ pé: “Ṣebí tòsí wa ni Dáfídì fara pa mọ́ sí,+ ní àwọn ibi tó ṣòroó dé ní Hóréṣì,+ lórí òkè Hákílà,+ tó wà ní gúúsù* Jéṣímónì.*+ 20 Ìgbàkígbà tó bá wù ọ́* láti wá, ìwọ ọba, o lè wá, a ó sì fà á lé ọba lọ́wọ́.”+ 21 Ni Sọ́ọ̀lù bá sọ pé: “Kí Jèhófà bù kún yín, nítorí ẹ ti ṣàánú mi. 22 Ẹ jọ̀wọ́, ẹ lọ bá mi wá ọ̀gangan ibi tó wà, kí ẹ wádìí lọ́wọ́ ẹni tó bá rí i níbẹ̀, nítorí mo ti gbọ́ pé alárèékérekè ni. 23 Ẹ fara balẹ̀ wá gbogbo ibi tó máa ń fara pa mọ́ sí, kí ẹ sì mú ẹ̀rí bọ̀ wá fún mi. Nígbà náà, màá bá yín lọ, tó bá sì wà ní ilẹ̀ náà, màá wá a jáde láàárín gbogbo ẹgbẹẹgbẹ̀rún* Júdà.”
24 Nítorí náà, wọ́n ṣáájú Sọ́ọ̀lù lọ sí Sífù,+ nígbà tí Dáfídì àti àwọn ọkùnrin rẹ̀ ṣì wà ní aginjù Máónì+ ní Árábà+ ní apá gúúsù Jéṣímónì. 25 Lẹ́yìn náà, Sọ́ọ̀lù àti àwọn ọkùnrin rẹ̀ wá a wá.+ Nígbà tí wọ́n sọ fún Dáfídì, ní kíá, ó lọ sí ibi àpáta,+ ó sì dúró sí aginjù Máónì. Nígbà tí Sọ́ọ̀lù gbọ́, ó lépa Dáfídì wọ inú aginjù Máónì. 26 Bí Sọ́ọ̀lù ṣe dé ẹ̀gbẹ́ kan òkè náà, Dáfídì àti àwọn ọkùnrin rẹ̀ wà ní ẹ̀gbẹ́ kejì òkè náà. Dáfídì ṣe kánkán+ kí ọwọ́ Sọ́ọ̀lù má bàa tẹ̀ ẹ́, àmọ́ Sọ́ọ̀lù àti àwọn ọkùnrin rẹ̀ túbọ̀ ń sún mọ́ Dáfídì àti àwọn ọkùnrin rẹ̀ láti gbá wọn mú.+ 27 Ṣùgbọ́n òjíṣẹ́ kan wá sọ́dọ̀ Sọ́ọ̀lù, ó sọ pé: “Tètè máa bọ̀, nítorí àwọn Filísínì ti wá kó ẹrù ní ilẹ̀ wa!” 28 Ni Sọ́ọ̀lù ò bá lépa Dáfídì mọ́,+ ó sì lọ gbéjà ko àwọn Filísínì. Ìdí nìyẹn tí wọ́n fi pe ibẹ̀ ní Àpáta Ìpínyà.
29 Lẹ́yìn náà, Dáfídì kúrò níbẹ̀, ó sì dúró sí àwọn ibi tó ṣòroó dé ní Ẹ́ń-gédì.+
24 Gbàrà tí Sọ́ọ̀lù pa dà lẹ́yìn àwọn Filísínì tó lé lọ, wọ́n sọ fún un pé: “Wò ó! Dáfídì wà ní aginjù Ẹ́ń-gédì.”+
2 Torí náà, Sọ́ọ̀lù kó ẹgbẹ̀rún mẹ́ta (3,000) ọkùnrin tí ó yàn látinú gbogbo Ísírẹ́lì, ó sì wá Dáfídì àti àwọn ọkùnrin rẹ̀ lọ sórí àwọn gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ àpáta tí àwọn ewúrẹ́ orí òkè máa ń wà. 3 Sọ́ọ̀lù dé ibi àwọn ọgbà àgùntàn tí wọ́n fi òkúta ṣe lójú ọ̀nà, níbi tí ihò kan wà, ó sì wọlé lọ láti tura,* àmọ́ Dáfídì àti àwọn ọkùnrin rẹ̀ jókòó sí inú ihò náà ní apá ẹ̀yìn.+ 4 Àwọn ọkùnrin Dáfídì sọ fún un pé: “Ọjọ́ yìí ni Jèhófà sọ fún ọ nípa rẹ̀ pé, ‘Wò ó! Màá fi ọ̀tá rẹ lé ọ lọ́wọ́,+ o lè ṣe ohunkóhun tó bá dára ní ojú rẹ sí i.’” Torí náà, Dáfídì dìde, ó sì rọra gé etí aṣọ àwọ̀lékè tí kò lápá tí Sọ́ọ̀lù wọ̀. 5 Àmọ́ lẹ́yìn náà, ọkàn* Dáfídì ń dá a lẹ́bi ṣáá,+ torí pé ó gé etí aṣọ àwọ̀lékè tí kò lápá tí Sọ́ọ̀lù wọ̀. 6 Ó sọ fún àwọn ọkùnrin rẹ̀ pé: “Jèhófà ò ní fẹ́ gbọ́ rárá pé mo ṣe irú nǹkan bẹ́ẹ̀ sí olúwa mi, ẹni àmì òróró Jèhófà, pé mo gbé ọwọ́ mi sókè sí i, torí ẹni àmì òróró Jèhófà ni.”+ 7 Ọ̀rọ̀ tí Dáfídì sọ yìí ló fi dá àwọn ọkùnrin tó wà pẹ̀lú rẹ̀ dúró,* kò sì gbà wọ́n láyè láti kọ lu Sọ́ọ̀lù. Àmọ́, Sọ́ọ̀lù dìde, ó kúrò nínú ihò náà, ó sì bá tiẹ̀ lọ.
8 Lẹ́yìn náà, Dáfídì dìde, ó jáde kúrò nínú ihò náà, ó sì nahùn pe Sọ́ọ̀lù, o ní: “Olúwa mi ọba!”+ Nígbà tí Sọ́ọ̀lù bojú wẹ̀yìn, Dáfídì tẹrí ba, ó sì dọ̀bálẹ̀. 9 Dáfídì sọ fún Sọ́ọ̀lù pé: “Kí nìdí tí o fi fetí sí àwọn tó ń sọ pé, ‘Wò ó! Dáfídì fẹ́ ṣe ọ́ ní jàǹbá’?+ 10 O ti fojú ara rẹ rí i lónìí bí Jèhófà ṣe fi ọ́ lé mi lọ́wọ́ nínú ihò. Àmọ́ nígbà tí ẹnì kan ní kí n pa ọ́,+ àánú rẹ ṣe mí, mo sì sọ pé, ‘Mi ò ní gbé ọwọ́ mi sókè sí olúwa mi, torí pé ẹni àmì òróró Jèhófà ni.’+ 11 Bàbá mi, wò ó, etí aṣọ àwọ̀lékè rẹ tí kò lápá rèé lọ́wọ́ mi; nígbà tí mo gé etí aṣọ àwọ̀lékè rẹ tí kò lápá, mi ò pa ọ́. Ṣé ìwọ náà rí i, ṣé o sì ti wá mọ̀ báyìí pé mi ò gbèrò láti ṣe ọ́ ní jàǹbá tàbí kí n dìtẹ̀ sí ọ? Mi ò ṣẹ̀ ọ́,+ àmọ́ ńṣe ni ò ń dọdẹ mi kiri láti gba ẹ̀mí* mi.+ 12 Kí Jèhófà ṣe ìdájọ́ láàárín èmi àti ìwọ,+ kí Jèhófà sì bá mi gbẹ̀san lára rẹ,+ àmọ́ mi ò ní jẹ́ gbé ọwọ́ mi sókè sí ọ.+ 13 Bí òwe àtijọ́ kan tó sọ pé, ‘Ẹni burúkú ló ń hùwà burúkú,’ àmọ́ ní tèmi, mi ò ní gbé ọwọ́ mi sókè sí ọ. 14 Ta tiẹ̀ ni ọba Ísírẹ́lì ń lé kiri? Ta ni ò ń lépa? Ṣé òkú ajá bíi tèmi yìí ni? Àbí ẹyọ eégbọn kan ṣoṣo?+ 15 Kí Jèhófà jẹ́ onídàájọ́, kí ó sì dájọ́ láàárín èmi àti ìwọ. Yóò rí i, yóò gba ẹjọ́ mi rò,+ yóò dá ẹjọ́ mi, yóò sì gbà mí lọ́wọ́ rẹ.”
16 Bí Dáfídì ṣe parí ọ̀rọ̀ tó sọ fún Sọ́ọ̀lù yìí, Sọ́ọ̀lù sọ pé: “Ṣé ohùn rẹ nìyí, Dáfídì ọmọ mi?”+ Sọ́ọ̀lù sì bẹ̀rẹ̀ sí í sunkún kíkankíkan. 17 Ó sọ fún Dáfídì pé: “Òdodo rẹ ju tèmi lọ, torí o ti ṣe dáadáa sí mi, àmọ́ mo ti fi ibi san án fún ọ.+ 18 Bẹ́ẹ̀ ni, o ti sọ ohun rere tí o ṣe lónìí fún mi bí o kò ṣe pa mí nígbà tí Jèhófà fi mí lé ọ lọ́wọ́.+ 19 Ta ló máa rí ọ̀tá rẹ̀ tí á sì jẹ́ kó faraare lọ? Jèhófà yóò fi ire san án fún ọ,+ nítorí ohun tí o ṣé fún mi lónìí. 20 Wò ó! Mo mọ̀ pé kò sí bí o kò ṣe ní di ọba tó máa ṣàkóso+ àti pé ìjọba Ísírẹ́lì máa pẹ́ lọ́wọ́ rẹ. 21 Ní báyìí, fi Jèhófà búra+ fún mi pé o ò ní pa àtọmọdọ́mọ* mi run àti pé o ò ní pa orúkọ mi rẹ́ kúrò nílé bàbá mi.”+ 22 Torí náà, Dáfídì búra fún Sọ́ọ̀lù, lẹ́yìn náà Sọ́ọ̀lù lọ sí ilé rẹ̀.+ Àmọ́ Dáfídì àti àwọn ọkùnrin rẹ̀ lọ sí ibi ààbò.+
25 Nígbà tó yá, Sámúẹ́lì+ kú; gbogbo Ísírẹ́lì kóra jọ kí wọ́n lè ṣọ̀fọ̀ rẹ̀, kí wọ́n sì sin ín sí ilé rẹ̀ ní Rámà.+ Ìgbà náà ni Dáfídì gbéra, ó sì lọ sí aginjù Páránì.
2 Ọkùnrin kan wà ní Máónì+ tó ń ṣiṣẹ́ ní Kámẹ́lì.*+ Ọkùnrin náà ní ọrọ̀ gan-an; ó ní ẹgbẹ̀rún mẹ́ta (3,000) àgùntàn àti ẹgbẹ̀rún kan (1,000) ewúrẹ́, ó sì ń rẹ́ irun àgùntàn rẹ̀ ní Kámẹ́lì. 3 Orúkọ ọkùnrin náà ni Nábálì,+ ìyàwó rẹ̀ sì ń jẹ́ Ábígẹ́lì.+ Ìyàwó yìí ní òye, ó sì rẹwà, ṣùgbọ́n ọkọ rẹ̀ tó jẹ́ ọmọ Kélẹ́bù+ le, ìwà rẹ̀ sì burú.+ 4 Dáfídì gbọ́ ní aginjù pé Nábálì ń rẹ́ irun àgùntàn rẹ̀. 5 Torí náà, Dáfídì rán ọ̀dọ́kùnrin mẹ́wàá sí i, Dáfídì sì sọ fún àwọn ọ̀dọ́kùnrin náà pé: “Ẹ lọ sí Kámẹ́lì, tí ẹ bá ti dé ọ̀dọ̀ Nábálì, kí ẹ sọ pé mo ní, ṣé àlàáfíà ni ó wà? 6 Lẹ́yìn náà, ẹ sọ pé, ‘Kí ẹ̀mí rẹ gùn,* kí àlàáfíà máa bá ìwọ àti agbo ilé rẹ gbé, kí gbogbo ohun tí o ní sì wà ní àlàáfíà. 7 Mo gbọ́ pé ò ń rẹ́ irun àwọn àgùntàn rẹ. Nígbà tí àwọn olùṣọ́ àgùntàn rẹ wà lọ́dọ̀ wa, a ò pa wọ́n lára,+ kò sì sí nǹkan wọn tó sọ nù ní gbogbo ìgbà tí wọ́n fi wà ní Kámẹ́lì. 8 Béèrè lọ́wọ́ àwọn ọ̀dọ́kùnrin rẹ, wọ́n á sì sọ fún ọ. Kí àwọn ọ̀dọ́kùnrin mi rí ojú rere rẹ, nítorí pé àkókò ayọ̀* ni a wá. Jọ̀wọ́ fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ àti Dáfídì ọmọ rẹ ní ohunkóhun tí o bá lè yọ̀ǹda.’”+
9 Ni àwọn ọ̀dọ́kùnrin Dáfídì bá lọ sọ gbogbo ọ̀rọ̀ yìí fún Nábálì ní orúkọ Dáfídì. Nígbà tí wọ́n parí ọ̀rọ̀ wọn, 10 Nábálì dá àwọn ìránṣẹ́ Dáfídì lóhùn pé: “Ta ni Dáfídì, ta sì ni ọmọ Jésè? Lóde òní, ọ̀pọ̀ àwọn ìránṣẹ́ ló ń sá kúrò lọ́dọ̀ ọ̀gá wọn.+ 11 Ṣé oúnjẹ mi àti omi mi àti ẹran tí mo pa fún àwọn tó ń bá mi rẹ́ irun àgùntàn ni kí n wá fún àwọn ọkùnrin tí mi ò mọ ibi tí wọ́n ti wá?”
12 Àwọn ọ̀dọ́kùnrin Dáfídì bá pa dà, wọ́n sì sọ gbogbo ọ̀rọ̀ yìí fún un. 13 Lójú ẹsẹ̀, Dáfídì sọ fún àwọn ọkùnrin rẹ̀ pé: “Kí kálukú yín sán idà rẹ̀!”+ Nítorí náà, gbogbo wọn sán idà wọn, Dáfídì náà sán idà rẹ̀, nǹkan bí ọgọ́rùn-ún mẹ́rin (400) ọkùnrin sì tẹ̀ lé Dáfídì, nígbà tí igba (200) ọkùnrin jókòó ti ẹrù wọn.
14 Ní àkókò yìí, ọ̀kan lára àwọn ìránṣẹ́ Nábálì ròyìn fún Ábígẹ́lì, ìyàwó Nábálì pé: “Wò ó! Dáfídì rán àwọn òjíṣẹ́ láti aginjù kí wọ́n wá wo àlàáfíà ọ̀gá wa, àmọ́ ṣe ló fi ìbínú sọ̀rọ̀ burúkú sí wọn.+ 15 Àwọn ọkùnrin náà ṣe dáadáa sí wa. Wọn ò pa wá lára rí, bẹ́ẹ̀ ni kò sí nǹkan wa kankan tó sọ nù ní gbogbo ìgbà tí a fi wà lọ́dọ̀ wọn ní pápá.+ 16 Wọ́n dà bí ògiri yí wa ká, ní ọ̀sán àti ní òru, ní gbogbo ìgbà tí a fi wà lọ́dọ̀ wọn, tí à ń tọ́jú àwọn àgùntàn. 17 Ní báyìí, pinnu ohun tí o máa ṣe, torí àjálù máa tó dé bá ọ̀gá wa àti gbogbo ilé rẹ̀,+ aláìníláárí*+ ni, kò sì sí ẹni tó lè bá a sọ̀rọ̀.”
18 Ni Ábígẹ́lì+ bá sáré mú igba (200) búrẹ́dì àti wáìnì ìṣà ńlá méjì àti àgùntàn márùn-ún tí wọ́n ti pa, tí wọ́n sì ti ṣètò rẹ̀ àti òṣùwọ̀n síà* márùn-ún àyangbẹ ọkà àti ọgọ́rùn-ún (100) ìṣù èso àjàrà gbígbẹ àti igba (200) ìṣù èso ọ̀pọ̀tọ́, ó sì kó gbogbo wọn sórí àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́.+ 19 Ó wá sọ fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pé: “Ẹ máa lọ níwájú mi; màá tẹ̀ lé yín.” Ṣùgbọ́n kò sọ nǹkan kan fún Nábálì ọkọ rẹ̀.
20 Bí ó ṣe ń lọ lórí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, òkè kan wà tí kò jẹ́ kó rí Dáfídì àti àwọn ọkùnrin rẹ̀ tí wọ́n ń bọ̀ lápá ọ̀dọ̀ rẹ̀, ló bá ṣe kòńgẹ́ wọn. 21 Dáfídì ti ń sọ pé: “Lásán ni mo ṣọ́ gbogbo nǹkan tí ọ̀gbẹ́ni yìí ní nínú aginjù. Kò sí ìkankan lára gbogbo ohun tó jẹ́ tirẹ̀ tó sọ nù,+ síbẹ̀ ibi ló fi san ire pa dà fún mi.+ 22 Kí Ọlọ́run gbẹ̀san lára àwọn ọ̀tá Dáfídì,* kó sì fìyà jẹ wọ́n gan-an tí mo bá jẹ́ kí ìkankan lára àwọn ọkùnrin* rẹ̀ ṣẹ́ kù títí di àárọ̀ ọ̀la.”
23 Nígbà tí Ábígẹ́lì tajú kán rí Dáfídì, ní kíá ó sọ̀ kalẹ̀ lórí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, ó kúnlẹ̀, ó sì dojú bolẹ̀ níwájú Dáfídì. 24 Ó kúnlẹ̀ síbi ẹsẹ̀ rẹ̀, ó sì sọ pé: “Olúwa mi, jẹ́ kí ẹ̀bi náà wà lórí mi; jẹ́ kí ìránṣẹ́bìnrin rẹ bá ọ sọ̀rọ̀, kí o sì fetí sí ọ̀rọ̀ tí ìránṣẹ́bìnrin rẹ fẹ́ sọ. 25 Kí olúwa mi jọ̀wọ́ má fiyè sí Nábálì ọkùnrin aláìníláárí+ yìí, nítorí bí orúkọ rẹ̀ ti jẹ́, ni òun náà jẹ́. Nábálì* ni orúkọ rẹ̀, ìwà òmùgọ̀ ló sì ń hù. Àmọ́ èmi ìránṣẹ́bìnrin rẹ kò rí àwọn ọ̀dọ́kùnrin tí olúwa mi rán. 26 Ní báyìí, olúwa mi, bí Jèhófà ti wà láàyè, tí ìwọ* náà sì wà láàyè, Jèhófà ni kò jẹ́ kí o+ jẹ̀bi ẹ̀jẹ̀,+ tí kò sì jẹ́ kí o fi ọwọ́ ara rẹ gbẹ̀san.* Kí àwọn ọ̀tá rẹ àti àwọn tí ó fẹ́ ṣe olúwa mi ní jàǹbá dà bíi Nábálì. 27 Jọ̀wọ́ jẹ́ kí a fún àwọn ọ̀dọ́kùnrin tó ń tẹ̀ lé olúwa mi+ ní ẹ̀bùn*+ tí ìránṣẹ́bìnrin rẹ mú wá fún olúwa mi. 28 Jọ̀wọ́, dárí ìṣìnà ìránṣẹ́bìnrin rẹ jì í, nítorí ó dájú pé Jèhófà máa ṣe ilé tó máa wà títí láé fún olúwa mi,+ nítorí àwọn ogun Jèhófà ni olúwa mi ń jà+ àti pé kò sí ìwà ibi kankan tí a rí lọ́wọ́ rẹ ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ.+ 29 Tí ẹnì kan bá dìde láti lépa rẹ, tí ó sì fẹ́ gba ẹ̀mí* rẹ, Jèhófà Ọlọ́run rẹ yóò fi ẹ̀mí* olúwa mi pa mọ́ sínú àpò ìwàláàyè lọ́dọ̀ rẹ̀. Ṣùgbọ́n, ní ti ẹ̀mí* àwọn ọ̀tá rẹ, òun yóò ta á jáde bí ìgbà tí èèyàn fi kànnàkànnà ta òkúta.* 30 Tí Jèhófà bá ti ṣe gbogbo ohun rere tí ó ṣèlérí fún olúwa mi, tí ó sì fi ọ́ ṣe olórí Ísírẹ́lì,+ 31 o ò ní banú jẹ́ tàbí kí o kábàámọ̀* nínú ọkàn rẹ pé o ta ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀ láìnídìí tàbí pé olúwa mi fi ọwọ́ ara rẹ̀ gbẹ̀san.*+ Nígbà tí Jèhófà bá bù kún olúwa mi, kí o rántí ìránṣẹ́bìnrin rẹ.”
32 Ni Dáfídì bá sọ fún Ábígẹ́lì pé: “Ìyìn ni fún Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì, tí ó rán ọ wá pàdé mi lónìí yìí! 33 Ìbùkún sì ni fún làákàyè rẹ! Kí Ọlọ́run bù kún ọ torí o ò jẹ́ kí n jẹ̀bi ẹ̀jẹ̀+ lónìí, o ò sì jẹ́ kí n fi ọwọ́ ara mi gbẹ̀san.* 34 Àìjẹ́ bẹ́ẹ̀, bí Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì tí ó dá mi dúró kí n má bàa ṣe ọ́ léṣe+ ti wà láàyè, ká ní o ò tètè wá pàdé mi+ ni, tó bá fi máa di àárọ̀ ọ̀la, kò ní sí ìkankan lára àwọn ọkùnrin* Nábálì tó máa ṣẹ́ kù.”+ 35 Ni Dáfídì bá gba ohun tó mú wá fún un, ó sì sọ fún un pé: “Máa lọ sí ilé rẹ ní àlàáfíà. Wò ó, mo ti gbọ́ ohun tí o sọ, màá sì ṣe ohun tí o béèrè.”
36 Lẹ́yìn náà, Ábígẹ́lì pa dà sọ́dọ̀ Nábálì, ó ń jẹ àsè lọ́wọ́ nínú ilé rẹ̀ bí ọba, inú Nábálì* ń dùn, ó sì ti mutí yó bìnàkò. Àmọ́ obìnrin náà kò sọ nǹkan kan fún un títí ilẹ̀ fi mọ́. 37 Ní àárọ̀ ọjọ́ kejì tí wáìnì ti dá lójú Nábálì, ìyàwó rẹ̀ sọ ohun tó ṣẹlẹ̀ fún un. Ọkàn rẹ̀ kú tipiri, ó sì sùn sílẹ̀ bí òkúta. 38 Ní nǹkan bí ọjọ́ mẹ́wàá lẹ́yìn náà, Jèhófà kọ lu Nábálì, ó sì kú.
39 Nígbà tí Dáfídì gbọ́ pé Nábálì ti kú, ó sọ pé: “Ẹ yin Jèhófà, ẹni tí ó bá mi dá ẹjọ́ mi+ nítorí àbùkù tí Nábálì fi kàn mí,+ tí kò sì jẹ́ kí ìránṣẹ́ rẹ̀ ṣe ohun búburú,+ Jèhófà sì ti mú kí ibi Nábálì dà lé e lórí!” Dáfídì wá ránṣẹ́ sí Ábígẹ́lì pé kó wá di ìyàwó òun. 40 Torí náà, àwọn ìránṣẹ́ Dáfídì wá sọ́dọ̀ Ábígẹ́lì ní Kámẹ́lì, wọ́n sì sọ fún un pé: “Dáfídì rán wa sí ọ pé kí o wá di ìyàwó òun.” 41 Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, ó dìde, ó dojú bolẹ̀, ó sì sọ pé: “Ẹrú rẹ obìnrin ṣe tán láti di ìránṣẹ́ tí á máa fọ ẹsẹ̀+ àwọn ìránṣẹ́ olúwa mi.” 42 Ìgbà náà ni Ábígẹ́lì+ yára dìde, ó gun kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀, márùn-ún lára àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ obìnrin sì ń rìn bọ̀ lẹ́yìn rẹ̀; ó bá àwọn òjíṣẹ́ Dáfídì lọ, ó sì di ìyàwó rẹ̀.
43 Dáfídì ti fẹ́ Áhínóámù+ láti Jésírẹ́lì,+ àwọn obìnrin méjèèjì sì di ìyàwó rẹ̀.+
44 Àmọ́ Sọ́ọ̀lù ti fi Míkálì+ ọmọ rẹ̀ tó jẹ́ ìyàwó Dáfídì fún Pálítì+ ọmọ Láíṣì, tó wá láti Gálímù.
26 Nígbà tó yá, àwọn ọkùnrin Sífù+ wá sọ́dọ̀ Sọ́ọ̀lù ní Gíbíà,+ wọ́n sọ pé: “Dáfídì fara pa mọ́ sórí òkè Hákílà tó dojú kọ Jéṣímónì.”*+ 2 Sọ́ọ̀lù bá dìde, òun àti ẹgbẹ̀rún mẹ́ta (3,000) àṣàyàn ọkùnrin ní Ísírẹ́lì sì lọ sí aginjù Sífù láti wá Dáfídì nínú aginjù náà.+ 3 Sọ́ọ̀lù pàgọ́ sẹ́gbẹ̀ẹ́ ọ̀nà lórí òkè Hákílà tó dojú kọ Jéṣímónì. Nígbà náà, Dáfídì ń gbé ní aginjù, ó sì gbọ́ pé Sọ́ọ̀lù ti wá òun wá sínú aginjù náà. 4 Torí náà, Dáfídì rán àwọn amí kí wọ́n lè lọ wò ó bóyá Sọ́ọ̀lù ti wá lóòótọ́. 5 Lẹ́yìn náà, Dáfídì lọ sí ibi tí Sọ́ọ̀lù pàgọ́ sí, Dáfídì sì rí ibi tí Sọ́ọ̀lù àti Ábínérì+ ọmọ Nérì olórí ọmọ ogun rẹ̀ sùn sí; Sọ́ọ̀lù sùn sílẹ̀ ní gbàgede ibùdó pẹ̀lú àwọn ọmọ ogun tó dó yí i ká. 6 Ìgbà náà ni Dáfídì sọ fún Áhímélékì ọmọ Hétì+ àti Ábíṣáì+ ọmọ Seruáyà,+ ẹ̀gbọ́n Jóábù pé: “Ta ló máa tẹ̀ lé mi lọ sí ibùdó lọ́dọ̀ Sọ́ọ̀lù?” Ábíṣáì fèsì pé: “Màá tẹ̀ lé ọ.” 7 Ni Dáfídì àti Ábíṣáì bá lọ sọ́dọ̀ àwọn ọmọ ogun náà lóru, wọ́n sì rí Sọ́ọ̀lù tó sùn sílẹ̀ ní gbàgede ibùdó, tó fi ọ̀kọ̀ rẹ̀ gúnlẹ̀ síbi orí rẹ̀; Ábínérì àti àwọn ọmọ ogun sì sùn yí i ká.
8 Ábíṣáì wá sọ fún Dáfídì pé: “Ọlọ́run ti fi ọ̀tá rẹ lé ọ lọ́wọ́ lónìí.+ Ní báyìí, jọ̀wọ́, jẹ́ kí n fi ọ̀kọ̀ gún un mọ́lẹ̀ lẹ́ẹ̀kan péré, mi ò ní ṣe é lẹ́ẹ̀mejì.” 9 Àmọ́, Dáfídì sọ fún Ábíṣáì pé: “Má ṣe é ní jàǹbá, ṣé ẹnì kan lè gbé ọwọ́ rẹ̀ sókè sí ẹni àmì òróró Jèhófà,+ kó má sì jẹ̀bi?”+ 10 Dáfídì ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ, ó ní: “Bí Jèhófà ti wà láàyè, Jèhófà fúnra rẹ̀ ló máa mú un balẹ̀,+ ó sì lè kú lọ́jọ́ kan+ tàbí kó lọ sójú ogun kó sì kú síbẹ̀.+ 11 Jèhófà ò ní fẹ́ gbọ́ rárá pé mo gbé ọwọ́ mi sókè sí ẹni àmì òróró Jèhófà!+ Ní báyìí, jọ̀wọ́ jẹ́ ká mú ọ̀kọ̀ àti ìgò omi tó wà níbi orí rẹ̀, kí a sì máa bá tiwa lọ.” 12 Torí náà, Dáfídì mú ọ̀kọ̀ àti ìgò omi tó wà níbi orí Sọ́ọ̀lù, wọ́n sì lọ. Kò sí ẹni tó rí wọn,+ bẹ́ẹ̀ ni ẹnì kankan ò kíyè sí wọn, kò tiẹ̀ sí ẹni tó jí, gbogbo wọn ti sùn lọ, nítorí oorun àsùnwọra láti ọ̀dọ̀ Jèhófà ni ó kùn wọ́n. 13 Ìgbà náà ni Dáfídì sọdá sí òdìkejì, ó dúró sórí òkè ní òkèèrè, àyè tó wà láàárín wọn sì pọ̀ gan-an.
14 Dáfídì nahùn pe àwọn ọmọ ogun náà àti Ábínérì+ ọmọ Nérì, ó ní: “Ábínérì, ṣé o ò ní dáhùn ni?” Ábínérì dáhùn pé: “Ìwọ ta ló ń pe ọba?” 15 Dáfídì sọ fún Ábínérì pé: “Ṣebí ọkùnrin ni ọ́? Ta sì ni ó dà bí rẹ ní Ísírẹ́lì? Kí wá nìdí tó ò fi máa ṣọ́ olúwa rẹ ọba? Torí ọ̀kan lára àwọn ọmọ ogun wọlé wá láti pa olúwa rẹ ọba.+ 16 Ohun tí o ṣe yìí kò dára. Bí Jèhófà ti wà láàyè, ikú tọ́ sí yín, torí ẹ ò ṣọ́ olúwa yín, ẹni àmì òróró Jèhófà.+ Ní báyìí, ẹ wò yí ká! Ibo ni ọ̀kọ̀ ọba àti ìgò omi+ tó wà níbi orí rẹ̀ wà?”
17 Sọ́ọ̀lù wá mọ̀ pé ohùn Dáfídì ni, ó sọ pé: “Ṣé ohùn rẹ nìyí, Dáfídì ọmọ mi?”+ Dáfídì fèsì pé: “Ohùn mi ni, olúwa mi ọba.” 18 Ó tún sọ pé: “Kí ló dé tí olúwa mi fi ń lépa ìránṣẹ́ rẹ̀,+ kí ni mo ṣe, kí sì ni ẹ̀bi mi?+ 19 Kí olúwa mi ọba jọ̀wọ́ fetí sí ọ̀rọ̀ ìránṣẹ́ rẹ̀: Tó bá jẹ́ pé Jèhófà ni ó fi sí ọ lọ́kàn láti máa lépa mi, kí ó gba* ọrẹ ọkà mi. Àmọ́ tó bá jẹ́ pé àwọn èèyàn ló fi sí ọ lọ́kàn,+ ègún ni fún wọn níwájú Jèhófà, torí pé wọ́n ti lé mi jáde lónìí, kí n má bàa ní ìpín nínú ogún Jèhófà,+ wọ́n ń sọ pé, ‘Lọ, kí o sì sin àwọn ọlọ́run míì!’ 20 Torí náà, má ṣe jẹ́ kí ẹ̀jẹ̀ mi kán sórí ilẹ̀ tí kò sí níwájú Jèhófà, nítorí ọba Ísírẹ́lì ti jáde lọ wá ẹyọ eégbọn kan ṣoṣo,+ àfi bíi pé ẹyẹ àparò ló ń lé lórí àwọn òkè.”
21 Ni Sọ́ọ̀lù bá sọ pé: “Mo ti ṣẹ̀.+ Pa dà wá, Dáfídì ọmọ mi, mi ò ní ṣe ọ́ ní jàǹbá mọ́, torí pé o ka ẹ̀mí* mi sí ohun iyebíye+ lónìí yìí. Òótọ́ ni pé mo ti hùwà òmùgọ̀, mo sì ti ṣe àṣìṣe ńlá.” 22 Dáfídì dáhùn pé: “Ọ̀kọ̀ ọba rèé. Jẹ́ kí ọ̀kan lára àwọn ọ̀dọ́kùnrin rẹ sọdá wá mú un. 23 Jèhófà ló máa san òdodo àti ìṣòtítọ́ kálukú+ pa dà fún un, torí pé Jèhófà fi ọ́ lé mi lọ́wọ́ lónìí, àmọ́ mi ò fẹ́ gbé ọwọ́ mi sókè sí ẹni àmì òróró Jèhófà.+ 24 Wò ó! Bí ẹ̀mí* rẹ ṣe ṣeyebíye sí mi lónìí, bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ̀mí* mi ṣeyebíye lójú Jèhófà, kí ó sì gbà mí nínú gbogbo wàhálà.”+ 25 Sọ́ọ̀lù dá Dáfídì lóhùn pé: “Kí Ọlọ́run bù kún ọ, Dáfídì ọmọ mi. Ó dájú pé wàá gbé àwọn ohun ńlá ṣe, wàá sì borí.”+ Ìgbà náà ni Dáfídì bá tiẹ̀ lọ, Sọ́ọ̀lù sì pa dà sí àyè rẹ̀.+
27 Àmọ́ Dáfídì sọ nínú ọkàn rẹ̀ pé: “Lọ́jọ́ kan, Sọ́ọ̀lù máa pa mí. Ohun tó máa dáa jù ni pé kí n sá lọ+ sí ilẹ̀ àwọn Filísínì; ìgbà yẹn ni Sọ́ọ̀lù á jáwọ́ nínú wíwá mi kiri ní gbogbo ìpínlẹ̀ Ísírẹ́lì,+ màá sì bọ́ lọ́wọ́ rẹ̀.” 2 Ni Dáfídì àti ọgọ́rùn-ún mẹ́fà (600) ọkùnrin+ tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ bá gbéra, wọ́n sì lọ sọ́dọ̀ Ákíṣì+ ọmọ Máókì, ọba Gátì. 3 Dáfídì dúró sọ́dọ̀ Ákíṣì ní Gátì, òun àti àwọn ọkùnrin rẹ̀, kálukú pẹ̀lú agbo ilé rẹ̀. Àwọn ìyàwó Dáfídì méjèèjì sì wà pẹ̀lú rẹ̀, Áhínóámù+ ará Jésírẹ́lì àti Ábígẹ́lì,+ opó Nábálì, ará Kámẹ́lì. 4 Nígbà tí wọ́n sọ fún Sọ́ọ̀lù pé Dáfídì ti sá lọ sí Gátì, kò tún wá a kiri mọ́.+
5 Nígbà náà, Dáfídì sọ fún Ákíṣì pé: “Tí mo bá rí ojú rere rẹ, jẹ́ kí wọ́n fún mi ní àyè nínú ọ̀kan lára àwọn ìlú tó wà ní ìgbèríko, kí n lè máa gbé ibẹ̀. Kí nìdí tí ìránṣẹ́ rẹ á fi máa bá ọ gbé nínú ìlú ọba?” 6 Torí náà, Ákíṣì fún un ní Síkílágì+ ní ọjọ́ yẹn. Ìdí nìyẹn tí Síkílágì fi jẹ́ ti àwọn ọba Júdà títí di òní yìí.
7 Àkókò* tí Dáfídì fi gbé ní ìgbèríko àwọn Filísínì jẹ́ ọdún kan àti oṣù mẹ́rin.+ 8 Dáfídì máa ń jáde lọ pẹ̀lú àwọn ọkùnrin rẹ̀ kí wọ́n lè kó nǹkan àwọn ará Géṣúrì+ àti àwọn Gísì àti àwọn ọmọ Ámálékì,+ nítorí wọ́n ń gbé ilẹ̀ tí ó lọ láti Télámù títí dé Ṣúrì+ àti títí dé ilẹ̀ Íjíbítì. 9 Nígbà tí Dáfídì bá lọ gbéjà ko ilẹ̀ náà, kì í dá ọkùnrin tàbí obìnrin sí,+ àmọ́ á kó àwọn agbo ẹran àti ọ̀wọ́ ẹran àti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ àti ràkúnmí àti aṣọ, lẹ́yìn náà, á wá pa dà sọ́dọ̀ Ákíṣì. 10 Ákíṣì á béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé: “Ibo ni ẹ ti lọ kó nǹkan lónìí?” Dáfídì á dáhùn pé: “Apá gúúsù* Júdà”+ tàbí “Apá gúúsù àwọn ọmọ Jéráméélì”+ tàbí “Apá gúúsù àwọn Kénì”+ ni. 11 Dáfídì kì í dá ọkùnrin tàbí obìnrin kankan sí tó máa mú wá sí Gátì, á sọ pé: “Kí wọ́n má bàa rojọ́ wa fún wọn pé, ‘Ohun tí Dáfídì ṣe nìyí.’” (Bí ó sì ṣe máa ń ṣe nìyẹn ní gbogbo ìgbà tó fi ń gbé ní ìgbèríko àwọn Filísínì.) 12 Nítorí náà, Ákíṣì gba Dáfídì gbọ́, ó sì ń sọ fún ara rẹ̀ pé: ‘Ó dájú pé ó ti di ẹni ìkórìíra láàárín àwọn èèyàn rẹ̀ Ísírẹ́lì, torí náà, á máa jẹ́ ìránṣẹ́ mi títí lọ.’
28 Nígbà yẹn, àwọn Filísínì kó àwọn ọmọ ogun wọn jọ láti bá Ísírẹ́lì jà.+ Nítorí náà, Ákíṣì sọ fún Dáfídì pé: “Ṣé o mọ̀ pé ìwọ àti àwọn ọkùnrin rẹ máa bá mi lọ jagun?”+ 2 Dáfídì bá sọ fún Ákíṣì pé: “Ìwọ náà mọ ohun tí ìránṣẹ́ rẹ máa ṣe.” Ni Ákíṣì bá sọ fún Dáfídì pé: “Ìdí nìyẹn tí màá fi yàn ọ́ ṣe ẹ̀ṣọ́ tí á máa ṣọ́ mi nígbà gbogbo.”*+
3 Lákòókò yìí, Sámúẹ́lì ti kú, gbogbo Ísírẹ́lì ti ṣọ̀fọ̀ rẹ̀, wọ́n sì ti sin ín sí Rámà ìlú rẹ̀.+ Sọ́ọ̀lù sì ti mú àwọn abẹ́mìílò àti àwọn woṣẹ́woṣẹ́ kúrò ní ilẹ̀ náà.+
4 Àwọn Filísínì kóra jọ, wọ́n lọ, wọ́n sì pabùdó sí Ṣúnémù.+ Nítorí náà, Sọ́ọ̀lù kó gbogbo Ísírẹ́lì jọ, wọ́n sì pabùdó sí Gíbóà.+ 5 Nígbà tí Sọ́ọ̀lù rí ibùdó àwọn Filísínì, ẹ̀rù bà á, àyà rẹ̀ sì já gan-an.+ 6 Bí Sọ́ọ̀lù tilẹ̀ ń wádìí lọ́dọ̀ Jèhófà,+ Jèhófà kò dá a lóhùn rárá, ì báà jẹ́ nípasẹ̀ àlá tàbí nípasẹ̀ Úrímù + tàbí àwọn wòlíì. 7 Níkẹyìn, Sọ́ọ̀lù sọ fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pé: “Ẹ bá mi wá obìnrin kan tí ó jẹ́ abẹ́mìílò,+ màá lọ wádìí lọ́wọ́ rẹ̀.” Àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ sọ fún un pé: “Wò ó! Obìnrin kan tí ó jẹ́ abẹ́mìílò wà ní Ẹ́ń-dórì.”+
8 Nítorí náà, Sọ́ọ̀lù pa ara dà, ó wọ aṣọ míì, ó sì lọ sọ́dọ̀ obìnrin náà ní òru pẹ̀lú méjì lára àwọn ọkùnrin rẹ̀. Ó ní: “Jọ̀wọ́, bá mi fi agbára ìbẹ́mìílò+ rẹ pe ẹni tí mo bá dárúkọ rẹ̀ fún ọ jáde.” 9 Ṣùgbọ́n, obìnrin náà sọ fún un pé: “Ó yẹ kí o mọ ohun tí Sọ́ọ̀lù ṣe dáadáa, bí ó ṣe mú àwọn abẹ́mìílò àti àwọn woṣẹ́woṣẹ́ kúrò ní ilẹ̀ yìí.+ Kí wá nìdí tí o fi fẹ́ dẹkùn mú mi* kí wọ́n lè pa mí?”+ 10 Sọ́ọ̀lù wá fi Jèhófà búra fún un pé: “Bí Jèhófà ti wà láàyè, o ò ní jẹ̀bi kankan lórí ọ̀rọ̀ yìí!” 11 Ni obìnrin náà bá sọ pé: “Ta ni kí n bá ọ pè jáde?” Ó fèsì pé: “Bá mi pe Sámúẹ́lì jáde.” 12 Nígbà tí obìnrin náà rí “Sámúẹ́lì,”*+ ó fi gbogbo agbára rẹ̀ ké jáde sí Sọ́ọ̀lù pé: “Kí ló dé tí o fi tàn mí? Ìwọ ni Sọ́ọ̀lù!” 13 Àmọ́ ọba sọ fún un pé: “Má bẹ̀rù, kí lo rí?” Obìnrin náà dá Sọ́ọ̀lù lóhùn pé: “Mo rí ẹnì kan tó dà bí ọlọ́run tó ń jáde bọ̀ láti inú ilẹ̀.” 14 Ní kíá, ó béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé: “Báwo ló ṣe rí?” Ó fèsì pé: “Ọkùnrin arúgbó kan ló ń jáde bọ̀, ó sì wọ aṣọ àwọ̀lékè tí kò lápá.”+ Sọ́ọ̀lù wá mọ̀ pé “Sámúẹ́lì” ni, ó tẹrí ba, ó sì dọ̀bálẹ̀.
15 Ìgbà náà ni “Sámúẹ́lì” sọ fún Sọ́ọ̀lù pé: “Kí ló dé tí o fi ń yọ mí lẹ́nu, tí o ní kí wọ́n pè mí jáde?” Sọ́ọ̀lù fèsì pé: “Mo wà nínú wàhálà ńlá. Àwọn Filísínì ń bá mi jà, Ọlọ́run sì ti fi mí sílẹ̀, kò dá mi lóhùn mọ́, ì báà jẹ́ nípasẹ̀ àwọn wòlíì tàbí nípasẹ̀ àlá;+ ìdí nìyẹn tí mo fi ń pè ọ́, kí o lè jẹ́ kí n mọ ohun tó yẹ kí n ṣe.”+
16 “Sámúẹ́lì” bá sọ pé: “Kí nìdí tí o fi ń wádìí lọ́dọ̀ mi ní báyìí tí Jèhófà ti fi ọ́ sílẹ̀,+ tó sì ti wá di ọ̀tá rẹ? 17 Jèhófà yóò ṣe ohun tí ó ti gbẹnu mi sọ: Jèhófà máa fa ìjọba náà ya kúrò lọ́wọ́ rẹ, á sì fún Dáfídì tí ó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn èèyàn rẹ.+ 18 Nítorí pé o kò ṣègbọràn sí ohùn Jèhófà, Ámálékì+ tó ń múnú bí i gan-an ni o kò sì pa run, ìdí nìyẹn tí Jèhófà fi ṣe báyìí sí ọ lónìí. 19 Jèhófà tún máa fi ìwọ àti Ísírẹ́lì lé àwọn Filísínì lọ́wọ́.+ Ní ọ̀la, ìwọ+ àti àwọn ọmọ rẹ+ yóò wà pẹ̀lú mi. Jèhófà sì máa tún fi àwọn ọmọ ogun Ísírẹ́lì lé àwọn Filísínì lọ́wọ́.”+
20 Ní kíá, Sọ́ọ̀lù nà gbalaja sórí ilẹ̀, ẹ̀rù sì bà á gan-an nítorí ọ̀rọ̀ “Sámúẹ́lì.” Kò sì sí okun kankan nínú rẹ̀ mọ́, torí pé kò tíì jẹun ní gbogbo ọ̀sán àti ní gbogbo òru. 21 Nígbà tí obìnrin náà wá bá Sọ́ọ̀lù, tó sì rí i pé ìdààmú ti bá a gan-an, ó sọ fún un pé: “Wò ó, ìránṣẹ́ rẹ ti ṣe ohun tí o sọ, mo ti fi ẹ̀mí mi wewu,*+ mo sì ṣe ohun tí o ní kí n ṣe. 22 Ní báyìí, jọ̀wọ́ gbọ́ ohun tí ìránṣẹ́ rẹ fẹ́ sọ. Jẹ́ kí n gbé oúnjẹ díẹ̀ síwájú rẹ, kí o lè jẹun, kí o sì ní okun nígbà tí o bá ń lọ.” 23 Ṣùgbọ́n ó kọ̀, ó sì sọ pé: “Mi ò ní jẹun.” Àmọ́, àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ àti obìnrin náà ń rọ̀ ọ́. Níkẹyìn, ó gbọ́ tiwọn, ó dìde nílẹ̀, ó sì jókòó sórí ibùsùn. 24 Obìnrin náà ní ọmọ màlúù àbọ́sanra kan nílé, torí náà ó sáré pa á,* ó bu ìyẹ̀fun, ó pò ó, ó sì fi ṣe búrẹ́dì aláìwú. 25 Ó wá gbé e fún Sọ́ọ̀lù àti àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀, wọ́n sì jẹun. Lẹ́yìn ìyẹn, wọ́n gbéra, wọ́n sì lọ ní òru yẹn.+
29 Àwọn Filísínì+ kó gbogbo ọmọ ogun wọn jọ sí Áfékì, nígbà tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì dó sẹ́gbẹ̀ẹ́ ìsun tí ó wà ní Jésírẹ́lì.+ 2 Àwọn alákòóso Filísínì ń kọjá lọ pẹ̀lú ọgọ́rọ̀ọ̀rún àti ẹgbẹẹgbẹ̀rún wọn, Dáfídì àti àwọn ọkùnrin rẹ̀ sì ń rìn bọ̀ lẹ́yìn pẹ̀lú Ákíṣì.+ 3 Àmọ́ àwọn ìjòyè Filísínì sọ pé: “Kí ni àwọn Hébérù yìí ń wá níbí?” Ákíṣì dá àwọn ìjòyè Filísínì lóhùn pé: “Dáfídì ìránṣẹ́ Sọ́ọ̀lù ọba Ísírẹ́lì rèé, ó ti tó ọdún kan tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ+ tí ó ti wà lọ́dọ̀ mi. Mi ò rí ohun tí kò tọ́ lọ́wọ́ rẹ̀ láti ọjọ́ tí ó ti sá wá sọ́dọ̀ mi títí di òní yìí.” 4 Àmọ́ inú bí àwọn ìjòyè Filísínì sí Ákíṣì gan-an, wọ́n sì sọ fún un pé: “Ní kí ọkùnrin náà pa dà.+ Kó pa dà sí àyè tí o yàn án sí. Má ṣe jẹ́ kó bá wa lọ sójú ogun, kó má bàa yíjú pa dà sí wa lójú ogun.+ Ọ̀nà wo ni ì bá tún gbà wá ojú rere olúwa rẹ̀ ju pé kó fi orí àwọn èèyàn wa lé e lọ́wọ́? 5 Ṣé kì í ṣe Dáfídì tí wọ́n kọrin fún, tí wọ́n sì ń jó fún nìyí, tí wọ́n ń sọ pé:
‘Sọ́ọ̀lù ti pa ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọ̀tá,
Àmọ́ Dáfídì pa ẹgbẹẹgbàárùn-ún ọ̀tá’?”+
6 Nítorí náà, Ákíṣì+ pe Dáfídì, ó sì sọ fún un pé: “Bí Jèhófà ti wà láàyè, olóòótọ́ ni ọ́, inú mi sì dùn sí i pé kí o bá àwọn ọmọ ogun mi jáde ogun,+ torí mi ò rí ohun tí kò tọ́ lọ́wọ́ rẹ láti ọjọ́ tí o ti dé ọ̀dọ̀ mi títí di òní yìí.+ Àmọ́ àwọn alákòóso kò fọkàn tán ọ.+ 7 Torí náà, pa dà ní àlàáfíà, má sì ṣe ohunkóhun tí á bí àwọn alákòóso Filísínì nínú.” 8 Àmọ́, Dáfídì sọ fún Ákíṣì pé: “Kí ló dé? Kí ni mo ṣe? Ohun tí kò tọ́ wo lo rí lọ́wọ́ ìránṣẹ́ rẹ láti ọjọ́ tí mo ti dé ọ̀dọ̀ rẹ títí di òní yìí? Kí nìdí tí mi ò fi lè tẹ̀ lé ọ, kí n sì bá àwọn ọ̀tá olúwa mi ọba jà?” 9 Ni Ákíṣì bá dá Dáfídì lóhùn pé: “Lójú tèmi, ìwà rẹ dára bíi ti áńgẹ́lì Ọlọ́run.+ Ṣùgbọ́n àwọn ìjòyè Filísínì ti sọ pé, ‘Má ṣe jẹ́ kí ó bá wa lọ sójú ogun.’ 10 Torí náà, dìde ní àárọ̀ kùtù pẹ̀lú àwọn ìránṣẹ́ olúwa rẹ tí ó bá ọ wá; kí ẹ gbéra, kí ẹ sì lọ ní àárọ̀ kùtù gbàrà tí ilẹ̀ bá ti mọ́.”
11 Torí náà, Dáfídì àti àwọn ọkùnrin rẹ̀ dìde ní àárọ̀ láti pa dà sí ilẹ̀ àwọn Filísínì, àwọn Filísínì sì lọ sí Jésírẹ́lì.+
30 Nígbà tí Dáfídì àti àwọn ọkùnrin rẹ̀ dé sí Síkílágì+ lọ́jọ́ kẹta, àwọn ọmọ Ámálékì+ ti wá kó ẹrù àwọn èèyàn ní gúúsù* àti ní Síkílágì, wọ́n ti gbéjà ko Síkílágì, wọ́n sì ti dáná sun ún. 2 Wọ́n ti kó àwọn obìnrin+ àti gbogbo àwọn tó wà nínú rẹ̀ lẹ́rú, látorí ẹni tó kéré jù dórí ẹni tó dàgbà jù. Wọn ò pa ẹnì kankan, àmọ́ wọ́n kó wọn, wọ́n sì bá tiwọn lọ. 3 Nígbà tí Dáfídì àti àwọn ọkùnrin rẹ̀ dé ìlú náà, wọ́n rí i tí ó ti jó kanlẹ̀, wọ́n sì ti kó àwọn ìyàwó wọn, àwọn ọmọkùnrin wọn pẹ̀lú àwọn ọmọbìnrin wọn lẹ́rú. 4 Ni Dáfídì àti àwọn ọkùnrin tó wà pẹ̀lú rẹ̀ bá bú sẹ́kún, wọ́n ń ké títí wọn ò fi lókun láti sunkún mọ́. 5 Àwọn ìyàwó Dáfídì méjèèjì ni wọ́n ti kó lẹ́rú, ìyẹn Áhínóámù ará Jésírẹ́lì àti Ábígẹ́lì opó Nábálì ará Kámẹ́lì.+ 6 Ìdààmú bá Dáfídì gan-an, torí àwọn ọkùnrin náà ń sọ pé àwọn máa sọ ọ́ lókùúta, torí inú bí gbogbo àwọn ọkùnrin náà gan-an, nítorí àwọn ọmọkùnrin wọn àti àwọn ọmọbìnrin wọn tí wọ́n kó lọ. Àmọ́ Dáfídì fún ara rẹ̀ lókun látọ̀dọ̀ Jèhófà Ọlọ́run rẹ̀.+
7 Ìgbà náà ni Dáfídì sọ fún àlùfáà Ábíátárì+ ọmọ Áhímélékì pé: “Jọ̀wọ́, mú éfódì wá.”+ Torí náà, Ábíátárì mú éfódì wá fún Dáfídì. 8 Dáfídì wádìí lọ́dọ̀ Jèhófà+ pé: “Ṣé kí n lépa àwọn jàǹdùkú* yìí? Ṣé màá lé wọn bá?” Ó sọ fún un pé: “Lépa wọn, torí ó dájú pé wàá lé wọn bá, wàá sì gba àwọn èèyàn rẹ pa dà.”+
9 Ní kíá, Dáfídì àti ọgọ́rùn-ún mẹ́fà (600) ọkùnrin+ tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ gbéra, wọ́n sì lọ títí dé Àfonífojì Bésórì, ibẹ̀ ni àwọn kan lára wọn dúró sí. 10 Dáfídì àti ọgọ́rùn-ún mẹ́rin (400) ọkùnrin ń lé wọn lọ, àmọ́ igba (200) ọkùnrin tí ó ti rẹ̀ débi pé wọn ò lè sọdá Àfonífojì Bésórì dúró síbẹ̀.+
11 Wọ́n rí ọkùnrin ará Íjíbítì kan nínú pápá, wọ́n sì mú un wá sọ́dọ̀ Dáfídì. Wọ́n fún un ní oúnjẹ jẹ, wọ́n sì fún un ní omi mu, 12 wọ́n tún fún un ní ègé ìṣù èso ọ̀pọ̀tọ́ àti ìṣù èso àjàrà gbígbẹ méjì. Lẹ́yìn tó jẹun tán, okun rẹ̀ pa dà,* torí kò tíì jẹ oúnjẹ kankan tàbí kó fẹnu kan omi láti ọ̀sán mẹ́ta àti òru mẹ́ta sẹ́yìn. 13 Dáfídì wá béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé: “Ìránṣẹ́ ta ni ọ́, ibo lo sì ti wá?” Ó dáhùn pé: “Ìránṣẹ́ tó jẹ́ ará Íjíbítì ni mí, mo sì jẹ́ ẹrú ọkùnrin ọmọ Ámálékì kan, ṣùgbọ́n ọ̀gá mi fi mí sílẹ̀ ní ọjọ́ mẹ́ta sẹ́yìn torí pé mo ṣàìsàn. 14 A kó ẹrù àwọn tó wà ní gúúsù* àwọn Kérétì+ àti ní ìpínlẹ̀ Júdà àti ní gúúsù* Kélẹ́bù,+ a sì dáná sun Síkílágì.” 15 Ni Dáfídì bá sọ fún un pé: “Ṣé wàá mú mi lọ sọ́dọ̀ àwọn jàǹdùkú* náà?” Ó fèsì pé: “Tí o bá lè fi Ọlọ́run búra fún mi pé o ò ní pa mí àti pé o ò ní fà mí lé ọ̀gá mi lọ́wọ́, màá mú ọ lọ bá àwọn jàǹdùkú* náà.”
16 Torí náà, ó mú un lọ síbi tí wọ́n tẹ́ rẹrẹ sí, tí wọ́n ń jẹ, tí wọ́n ń mu, tí wọ́n sì ń ṣe àríyá nítorí gbogbo ẹrù púpọ̀ tí wọ́n rí kó ní ilẹ̀ àwọn Filísínì àti ní ilẹ̀ Júdà. 17 Dáfídì wá bẹ̀rẹ̀ sí í pa wọ́n láti ìdájí títí di ìrọ̀lẹ́; kò sí ẹni tó yè bọ́ àfi ọgọ́rùn-ún mẹ́rin (400) ọkùnrin tó gun ràkúnmí sá lọ.+ 18 Dáfídì gba gbogbo ohun tí àwọn ọmọ Ámálékì ti kó pa dà,+ Dáfídì sì gba ìyàwó rẹ̀ méjèèjì sílẹ̀. 19 Kò sí ìkankan nínú nǹkan wọn tí wọn ò rí, látorí èyí tó kéré jù dórí èyí tó tóbi jù. Wọ́n gba àwọn ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin àti ẹrù wọn tí wọ́n kó;+ Dáfídì gba gbogbo ohun tí wọ́n kó pa dà. 20 Torí náà, Dáfídì kó gbogbo agbo ẹran àti ọ̀wọ́ ẹran náà, èyí tí wọ́n ń dà lọ níwájú àwọn ẹran ọ̀sìn tiwọn. Wọ́n sọ pé: “Ẹrù tí Dáfídì kó nìyí.”
21 Nígbà náà, Dáfídì dé ọ̀dọ̀ igba (200) ọkùnrin tó rẹ̀ débi pé wọn ò lè tẹ̀ lé Dáfídì, tí wọ́n sì dúró sẹ́gbẹ̀ẹ́ Àfonífojì Bésórì,+ wọ́n jáde wá pàdé Dáfídì àti àwọn èèyàn tó wà pẹ̀lú rẹ̀. Nígbà tí Dáfídì sún mọ́ àwọn ọkùnrin náà, ó béèrè àlàáfíà wọn. 22 Àmọ́, gbogbo àwọn tó burú, tí wọn ò sì ní láárí lára àwọn ọkùnrin tó bá Dáfídì lọ sọ pé: “Torí pé wọn ò bá wa lọ, a ò ní fún wọn ní nǹkan kan lára ẹrù tí a kó pa dà, àfi kí kálukú mú ìyàwó àti àwọn ọmọ rẹ̀, kí wọ́n sì máa lọ.” 23 Àmọ́ Dáfídì sọ pé: “Ẹ má ṣe bẹ́ẹ̀, ẹ̀yin arákùnrin mi, ẹ wo ohun tí Jèhófà fún wa. Ó dáàbò bò wá, ó sì fi àwọn jàǹdùkú* tó wá sọ́dọ̀ wa lé wa lọ́wọ́.+ 24 Ta ló máa fara mọ́ ohun tí ẹ sọ yìí? Ohun tí a máa pín fún ẹni tó lọ sójú ogun náà la máa pín fún ẹni tó jókòó ti ẹrù.+ Kálukú ló máa gba ìpín tirẹ̀.”+ 25 Láti ọjọ́ náà lọ, ó sọ ọ́ di ìlànà àti òfin fún Ísírẹ́lì títí di òní yìí.
26 Nígbà tí Dáfídì pa dà sí Síkílágì, ó mú lára ẹrù tí wọ́n kó, ó sì fi ránṣẹ́ sí àwọn àgbààgbà Júdà tí wọ́n jẹ́ ọ̀rẹ́ rẹ̀, ó sọ pé: “Ẹ̀bùn* tiyín nìyí látinú ẹrù àwọn ọ̀tá Jèhófà tí a kó.” 27 Ó fi wọ́n ránṣẹ́ sí àwọn tó wà ní Bẹ́tẹ́lì,+ sí àwọn tó wà ní Rámótì ti Négébù* àti sí àwọn tó wà ní Játírì,+ 28 sí àwọn tó wà ní Áróérì, sí àwọn tó wà ní Sífúmótì àti sí àwọn tó wà ní Éṣítémóà,+ 29 sí àwọn tó wà ní Rákálì, sí àwọn tó wà ní ìlú àwọn ọmọ Jéráméélì+ àti sí àwọn tó wà nínú ìlú àwọn Kénì,+ 30 sí àwọn tó wà ní Hóómà,+ sí àwọn tó wà ní Bóráṣánì àti sí àwọn tó wà ní Átákì, 31 sí àwọn tó wà ní Hébúrónì+ àti sí gbogbo ibi tí Dáfídì àti àwọn ọkùnrin rẹ̀ máa ń lọ.
31 Nígbà náà, àwọn Filísínì ń bá Ísírẹ́lì jà.+ Àwọn ọkùnrin Ísírẹ́lì sá kúrò níwájú àwọn Filísínì, ọ̀pọ̀ lára wọn sì kú sórí Òkè Gíbóà.+ 2 Àwọn Filísínì sún mọ́ Sọ́ọ̀lù àti àwọn ọmọ rẹ̀, àwọn Filísínì sì pa Jónátánì,+ Ábínádábù àti Maliki-ṣúà, àwọn ọmọ Sọ́ọ̀lù.+ 3 Ìjà náà le mọ́ Sọ́ọ̀lù, ọwọ́ àwọn tafàtafà bà á, wọ́n sì dá ọgbẹ́ sí i lára yánnayànna.+ 4 Ni Sọ́ọ̀lù bá sọ fún ẹni tó ń bá a gbé ìhámọ́ra pé: “Fa idà rẹ yọ, kí o sì fi gún mi ní àgúnyọ, kí àwọn aláìdádọ̀dọ́*+ yìí má bàa wá gún mi ní àgúnyọ, kí wọ́n sì hùwà ìkà sí mi.”* Àmọ́, ẹni tó ń bá a gbé ìhámọ́ra kò fẹ́ ṣe bẹ́ẹ̀, nítorí ẹ̀rù bà á gan-an. Torí náà, Sọ́ọ̀lù mú idà, ó sì ṣubú lé e.+ 5 Nígbà tí ẹni tó ń bá a gbé ìhámọ́ra rí i pé Sọ́ọ̀lù ti kú,+ òun náà ṣubú lé idà tirẹ̀, ó sì kú pẹ̀lú rẹ̀. 6 Bí Sọ́ọ̀lù àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta àti ẹni tó ń bá a gbé ìhámọ́ra pẹ̀lú gbogbo àwọn ọkùnrin rẹ̀ ṣe kú pa pọ̀ ní ọjọ́ yẹn nìyẹn.+ 7 Nígbà tí àwọn èèyàn Ísírẹ́lì tó ń gbé ní agbègbè àfonífojì* àti agbègbè ilẹ̀ Jọ́dánì rí i pé àwọn ọkùnrin Ísírẹ́lì ti sá lọ àti pé Sọ́ọ̀lù àti àwọn ọmọ rẹ̀ ti kú, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í fi ìlú sílẹ̀, wọ́n sì sá lọ;+ lẹ́yìn náà, àwọn Filísínì wá, wọ́n sì ń gbé ibẹ̀.
8 Ní ọjọ́ kejì, nígbà tí àwọn Filísínì wá bọ́ àwọn nǹkan tó wà lára àwọn tí wọ́n pa, wọ́n rí Sọ́ọ̀lù àti àwọn ọmọ rẹ̀ mẹ́ta tí wọ́n ti kú sórí Òkè Gíbóà.+ 9 Wọ́n gé orí rẹ̀ kúrò, wọ́n bọ́ ìhámọ́ra rẹ̀, wọ́n sì ránṣẹ́ sí gbogbo ilẹ̀ àwọn Filísínì pé kí wọ́n ròyìn rẹ̀ ní àwọn ilé*+ òrìṣà wọn+ àti láàárín àwọn èèyàn náà. 10 Wọ́n wá gbé ìhámọ́ra rẹ̀ sínú ilé àwọn ère Áṣítórétì, wọ́n sì kan òkú rẹ̀ mọ́ ògiri Bẹti-ṣánì.+ 11 Nígbà tí àwọn tó ń gbé ní Jabeṣi-gílíádì+ gbọ́ ohun tí àwọn Filísínì ṣe sí Sọ́ọ̀lù, 12 gbogbo àwọn jagunjagun gbéra, wọ́n sì rìnrìn àjò ní gbogbo òru, wọ́n gbé òkú Sọ́ọ̀lù àti àwọn ọmọ rẹ̀ kúrò lára ògiri Bẹti-ṣánì. Wọ́n pa dà sí Jábéṣì, wọ́n sì sun wọ́n níbẹ̀. 13 Wọ́n wá kó egungun wọn,+ wọ́n sin wọ́n sábẹ́ igi támáríkì ní Jábéṣì,+ wọ́n sì fi ọjọ́ méje gbààwẹ̀.
Tàbí “láti Rámà, ó jẹ́ ará Súfì.”
Tàbí “forí balẹ̀.”
Ní Héb., “ti sé ilé ọmọ Hánà.”
Tàbí “lọ́kàn jẹ́?”
Ìyẹn, àgọ́ ìjọsìn.
Tàbí “Ọkàn Hánà gbọgbẹ́.”
Tàbí “Obìnrin tí ìnira ńlá bá ẹ̀mí rẹ̀ ni mí.”
Ní Héb., “rántí rẹ̀.”
Tàbí kó jẹ́, “Nígbà tó yá.”
Ó túmọ̀ sí “Orúkọ Ọlọ́run.”
Ní Héb., “Ohun tó bá dára ní ojú rẹ.”
Nǹkan bíi Lítà 22. Wo Àfikún B14.
Ó dà bíi jọ́ọ̀gì omi.
Tàbí “Bí ọkàn rẹ ti wà láàyè.”
Ó ṣe kedere pé Ẹlikénà ló ń tọ́ka sí.
Ní Héb., “Jèhófà ti gbé ìwo mi ga.” Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.
Ní Héb., “Ọrun.”
Ní Héb., “ti rọ dà nù.”
Tàbí “sọni di alààyè.”
Tàbí “Ṣìọ́ọ̀lù,” ìyẹn ibojì aráyé. Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.
Tàbí kó jẹ́, “ààtàn.”
Tàbí kó jẹ́, “Ẹ̀rù yóò ba àwọn tó ń bá Jèhófà jà.”
Tàbí “agbára.” Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.
Tàbí “ń sin.”
Tàbí “tí ọkàn rẹ bá fà sí.”
Ní Héb., “sán.”
Tàbí “aṣọ àtàtà.”
Tàbí kó jẹ́, “Ọlọ́run lè parí ìjà fún un.”
Tàbí kó jẹ́, “láti mú ẹbọ rú èéfín tùù sókè.”
Ní Héb., “àwọn ọmọkùnrin Ísírẹ́lì.”
Ní Héb., “tàpá sí ẹbọ mi.”
Ní Héb., “gé apá rẹ kúrò.”
Tàbí “mú kí ọkàn rẹ ṣàárẹ̀.”
Ìyẹn, àgọ́ ìjọsìn.
Ní Héb., “bọ́ sí ilẹ̀.”
Ní Héb., “tí Jèhófà fi ṣẹ́gun wa nípasẹ̀ àwọn Filísínì lónìí?”
Tàbí kó jẹ́, “láàárín.”
Tàbí “kò sì fọkàn sí i.”
Ó túmọ̀ sí “Ibo Ni Ògo Wà?”
Tàbí “tẹ́ńpìlì.”
Ní Héb., “Dágónì nìkan.”
Tàbí “ìdí yíyọ.”
Tàbí “ìdí yíyọ.”
Tàbí “wíìtì.”
Tàbí “pẹ̀tẹ́lẹ̀.”
Ní Héb., “àwọn 70 ọkùnrin àti àwọn 50,000 ọkùnrin.”
Tàbí “ṣèdárò.”
Ó túmọ̀ sí “Òkúta Ìrànlọ́wọ́.”
Ní Héb., “ó burú lójú Sámúẹ́lì.”
Tàbí “àwọn olùṣe lọ́fíńdà.”
Ní Héb., “ní etí.”
Ní Héb., “àwọn abo kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́.”
Ṣékélì kan jẹ́ gíráàmù 11.4. Wo Àfikún B14.
Ní Héb., “súre.”
Ní Héb., “ṣí Sámúẹ́lì létí.”
Tàbí “ṣèkáwọ́ àwọn èèyàn mi.”
Ní Héb., “gbogbo ohun tó wà lọ́kàn rẹ.”
Ìyẹn, ohun tí a fi amọ̀ ṣe tó dà bí ìgò ńlá.
Tàbí “fi ń pòwe.”
Tàbí “agboolé-agboolé.”
Ní Héb., “Ó sì wá dà bí ẹni tí kò lè sọ̀rọ̀.”
Tàbí “Fohùn ṣọ̀kan pẹ̀lú wa.”
Ní Héb., “Gíbíà ti Sọ́ọ̀lù.”
Ní Héb., “bí ọkùnrin kan.”
Ìyẹn, ní nǹkan bí aago méjì òru sí mẹ́fà àárọ̀.
Ní Héb., “fetí sí ohùn yín ní ti.”
Ní Héb., “lọ níwájú.”
Tàbí “owó mẹ́numọ́.”
Ní Héb., “ẹ ò rí nǹkan kan lọ́wọ́ mi.”
Tàbí “wíìtì.”
Tàbí “òtúbáńtẹ́.”
Tàbí “òtúbáńtẹ́.”
Tàbí “ní òtítọ́.”
Kò sí iye ọdún náà nínú ẹ̀dà ti èdè Hébérù ayé àtijọ́.
Tàbí “yàrá.”
Tàbí “yàn.”
Tàbí “tu Jèhófà lójú.”
Òṣùwọ̀n àtijọ́ kan, ó wúwo tó nǹkan bí ìdá méjì nínú mẹ́ta ṣékélì kan.
Tàbí “àwùjọ àwọn ọmọ ogun Filísínì tó wà ní àdádó.”
Tàbí “aláìkọlà.”
Ìyẹn, ìdajì oko tí màlúù méjì tí wọ́n so pọ̀ lè túlẹ̀ rẹ̀ ní ọjọ́ kan.
Ní Héb., “ní ọjọ́ yẹn.”
Ní Héb., “Fa ọwọ́ rẹ sẹ́yìn.”
Ní Héb., “búrẹ́dì.”
Ní Héb., “Gbogbo ilẹ̀.”
Ní Héb., “ojú rẹ̀ tàn yanran.”
Tàbí “ìtanùlẹ́gbẹ́.”
Ní Héb., “bí ojú mi ṣe tàn yanran.”
Tàbí “ìgbàlà.”
Ní Héb., “ra Jónátánì pa dà.”
Tàbí “ṣàánú wọn.”
Tàbí “yọ́nú sí Ágágì.”
Tàbí “Mo kẹ́dùn.”
Tàbí “fi ìyọ́nú hàn sí agbo ẹran àti ọ̀wọ́ ẹran tó dára jù.”
Ní Héb., “ère tẹ́ráfímù,” ìyẹn, àwọn òrìṣà ìdílé; òrìṣà.
Tàbí “kábàámọ̀.”
Tàbí “kábàámọ̀.”
Tàbí kó jẹ́, “Ágágì bá ń fi ìgboyà.”
Ní Héb., “ìkorò ikú.”
Tàbí “Jèhófà sì kẹ́dùn.”
Tàbí “ìránṣẹ́.”
Ní Héb., “àwọn ibùdó.”
Tàbí “Pẹ̀tẹ́lẹ̀.”
Gíga rẹ̀ jẹ́ nǹkan bíi mítà 2.9 (ẹsẹ̀ bàtà 9 ínǹṣì 5.75.) Wo Àfikún B14.
Irú èyí tí àwọn ọmọ ogun máa ń dé.
Nǹkan bíi kìlógíráàmù 57. Wo Àfikún B14.
Ìyẹn, ohun tí àwọn ọmọ ogun fi ń bo ojúgun.
Tàbí “ọ̀kọ̀ kékeré.”
Tàbí “olófì.”
Nǹkan bíi kìlógíráàmù 6.84. Wo Àfikún B14.
Tàbí “Mo pe ìlà ogun Ísírẹ́lì níjà.”
Nǹkan bíi Lítà 22. Wo Àfikún B14.
Ní Héb., “mílíìkì.”
Tàbí “Pẹ̀tẹ́lẹ̀.”
Tàbí “pe Ísírẹ́lì níjà.”
Tàbí “aláìkọlà.”
Tàbí “rẹ̀wẹ̀sì.”
Tàbí “ọkùnrin ogun.”
Tàbí “ní páárì ẹ̀rẹ̀kẹ́.” Ní Héb., “ní irùngbọ̀n.”
Tàbí “aláìkọlà.”
Tàbí “pe àwọn ìlà ogun Ọlọ́run alààyè níjà.”
Ní Héb., “lọ́wọ́ èékánná.”
Irú èyí tí àwọn ọmọ ogun máa ń dé.
Tàbí “ọ̀kọ̀ kékeré.”
Tàbí “pè níjà.”
Ní Héb., “Gbogbo ìjọ yìí.”
Tàbí “ọkàn rẹ.”
Tàbí “ọkàn Jónátánì fà mọ́ ọkàn Dáfídì.”
Tàbí “bí ọkàn ara rẹ̀.”
Tàbí “bí ọkàn ara rẹ̀.”
Tàbí “hùwà ọgbọ́n.”
Tàbí “bíi wòlíì.”
Ní Héb., “ó ń jáde lọ, ó sì ń wọlé níwájú àwọn èèyàn náà.”
Tàbí “hùwà ọgbọ́n.”
Tàbí “ọkọ ọmọ.”
Tàbí “ọkọ ọmọ.”
Tàbí “hùwà ọgbọ́n.”
Ní Héb., “ṣẹ.”
Tàbí “fi ọkàn rẹ̀ sí àtẹ́lẹwọ́ rẹ̀.”
Tàbí “rí ìgbàlà.”
Tàbí “Tí o kò bá jẹ́ kí ọkàn rẹ sá àsálà.”
Tàbí “wíńdò.”
Tàbí “òrìṣà ìdílé; òrìṣà.”
Tàbí “òrìṣà ìdílé; òrìṣà.”
Tàbí “pẹ̀lú aṣọ jáńpé lára.”
Tàbí “ọkàn.”
Tàbí “ọkàn rẹ.”
Tàbí “ọkàn rẹ.”
Tàbí “ọkàn ara.”
Ní Héb., “ní ọjọ́ iṣẹ́.”
Ní Héb., “ìhòòhò ìyá rẹ?”
Ní Héb., “nítorí pé ọmọ ikú ni.”
Ní Héb., “èso.”
Ní Héb., “èso.”
Tàbí “ní ìbálòpọ̀.”
Tàbí “Pẹ̀tẹ́lẹ̀.”
Ní Héb., “ní ọwọ́ wọn.”
Tàbí “ìkorò ọkàn.”
Tàbí “jẹ́ olóòótọ́.”
Ní Héb., “àwọn sárésáré.”
Tàbí “aṣọ àtàtà.”
Tàbí “ọkàn.”
Tàbí “ọkàn.”
Tàbí “ọkàn.”
Ní Héb., “tà á sọ́wọ́ mi.”
Tàbí kó jẹ́, “àwọn onílẹ̀.”
Tàbí kó jẹ́, “Ẹ̀rù ń ba Dáfídì torí pé.”
Tàbí “ọkàn.”
Ní Héb., “ó sì fún ọwọ́ rẹ̀ lókun nínú.”
Ní Héb., “ẹ̀gbẹ́ ọ̀tún.”
Tàbí kó jẹ́, “aṣálẹ̀; aginjù.”
Tàbí “wu ọkàn rẹ.”
Tàbí “agbo ilé.”
Ní Héb., “bo ẹsẹ̀ rẹ̀.”
Tàbí “ẹ̀rí ọkàn.”
Tàbí kó jẹ́, “tú àwọn ọkùnrin tó wà pẹ̀lú rẹ̀ ká.”
Tàbí “ọkàn.”
Ní Héb., “èso.”
Ìlú kan ní Júdà; ó yàtọ̀ sí Òkè Kámẹ́lì.
Tàbí “Kí o ní àlàáfíà.”
Ní Héb., “ọjọ́ rere.”
Tàbí “aláìdára fún ohunkóhun.”
Síà kan jẹ́ Lítà 7.33. Wo Àfikún B14.
Tàbí kó jẹ́, “lára Dáfídì.”
Ní Héb., “ẹnikẹ́ni tó ń tọ̀ sára ògiri.” Ọ̀rọ̀ Hébérù tí wọ́n fi ń pẹ̀gàn àwọn ọkùnrin.
Ó túmọ̀ sí “Òmùgọ̀; Òpònú.”
Tàbí “ọkàn rẹ.”
Tàbí “gba ara rẹ là.”
Ní Héb., “ìbùkún.”
Tàbí “ọkàn.”
Tàbí “ọkàn.”
Tàbí “ọkàn.”
Tàbí “ta òkúta láti inú kànnàkànnà.”
Ní Héb., “ta gọ̀ọ́gọ̀ọ́ tàbí kọsẹ̀.”
Tàbí “gba ara rẹ là.”
Tàbí “gba ara mi là.”
Ní Héb., “ẹnikẹ́ni tó ń tọ̀ sára ògiri.” Ọ̀rọ̀ Hébérù tí wọ́n fi ń pẹ̀gàn àwọn ọkùnrin.
Ní Héb., “ọkàn Nábálì.”
Tàbí kó jẹ́, “aṣálẹ̀; aginjù.”
Ní Héb., “gbóòórùn.”
Tàbí “ọkàn.”
Tàbí “ọkàn.”
Tàbí “ọkàn.”
Ní Héb., “Iye ọjọ́.”
Tàbí “Négébù.”
Ní Héb., “olùṣọ́ orí mi lọ́jọ́ gbogbo.”
Tàbí “ọkàn mi.”
Tàbí “ohun tó fara jọ Sámúẹ́lì.”
Tàbí “ọkàn mi sí ọwọ́ mi.”
Tàbí “fi í rúbọ.”
Tàbí “Négébù.”
Tàbí “akónilẹ́rù.”
Ní Héb., “ẹ̀mí rẹ̀ sọjí.”
Tàbí “Négébù.”
Tàbí “Négébù.”
Tàbí “akónilẹ́rù.”
Tàbí “akónilẹ́rù.”
Tàbí “akónilẹ́rù.”
Ní Héb., “Ìbùkún.”
Tàbí “gúúsù.”
Tàbí “aláìkọlà.”
Tàbí “ṣe mí ṣúkaṣùka.”
Tàbí “pẹ̀tẹ́lẹ̀.”
Tàbí “tẹ́ńpìlì.”