ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • nwt Ìṣípayá 1:1-22:21
  • Ìfihàn

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìfihàn
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
Ìfihàn

ÌFIHÀN ÈYÍ TÍ JÒHÁNÙ RÍ

1 Ìfihàn* látọ̀dọ̀ Jésù Kristi, èyí tí Ọlọ́run fún un,+ kó lè fi àwọn nǹkan tó gbọ́dọ̀ ṣẹlẹ̀ láìpẹ́ han àwọn ẹrú rẹ̀.+ Ó rán áńgẹ́lì rẹ̀ láti fi han ẹrú rẹ̀, Jòhánù,+ nípasẹ̀ àwọn àmì, 2 ẹni tó jẹ́rìí sí ọ̀rọ̀ tí Ọlọ́run fúnni àti sí ẹ̀rí tí Jésù Kristi jẹ́, kódà sí gbogbo ohun tó rí. 3 Aláyọ̀ ni ẹni tó ń ka àwọn ọ̀rọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ yìí sókè àti àwọn tó ń gbọ́, tí wọ́n sì ń pa àwọn ohun tí a kọ sínú rẹ̀ mọ́,+ torí àkókò tí a yàn ti sún mọ́.

4 Èmi Jòhánù ń kọ̀wé sí àwọn ìjọ méje+ tó wà ní ìpínlẹ̀ Éṣíà:

Kí ẹ ní inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí àti àlàáfíà látọ̀dọ̀ “Ẹni tó ti wà tipẹ́, tó wà báyìí, tó sì ń bọ̀”+ àti látọ̀dọ̀ ẹ̀mí méje+ tó wà níwájú ìtẹ́ rẹ̀ 5 àti látọ̀dọ̀ Jésù Kristi, “Ẹlẹ́rìí Olóòótọ́,”+ “àkọ́bí nínú àwọn òkú,”+ àti “Alákòóso àwọn ọba ayé.”+

Ẹni tó nífẹ̀ẹ́ wa,+ tó fi ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ dá wa sílẹ̀ nínú àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa+— 6 tó sì mú ká di ìjọba kan,+ àlùfáà+ fún Ọlọ́run àti Baba rẹ̀—àní, òun ni kí ògo àti agbára jẹ́ tirẹ̀ títí láé. Àmín.

7 Wò ó! Ó ń bọ̀ pẹ̀lú ìkùukùu,*+ gbogbo ojú sì máa rí i, títí kan àwọn tó gún un lọ́kọ̀; ìbànújẹ́ nítorí rẹ̀ sì máa mú kí gbogbo ẹ̀yà tó wà ní ayé lu ara wọn.+ Bẹ́ẹ̀ ni kó rí, Àmín.

8 Jèhófà* Ọlọ́run sọ pé, “Èmi ni Ááfà àti Ómégà,*+ Ẹni tó ti wà tipẹ́, tó wà báyìí, tó sì ń bọ̀, Olódùmarè.”+

9 Èmi Jòhánù, arákùnrin yín, tó bá yín pín nínú ìpọ́njú+ àti ìjọba+ àti ìfaradà+ ní ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú Jésù,+ mo wà ní erékùṣù tí wọ́n ń pè ní Pátímọ́sì torí mò ń sọ̀rọ̀ nípa Ọlọ́run, mo sì ń jẹ́rìí nípa Jésù. 10 Mo wà ní ọjọ́ Olúwa nípasẹ̀ ìmísí, mo sì gbọ́ ohùn kan lẹ́yìn mi tó rinlẹ̀ bíi ti kàkàkí, 11 ó sọ pé: “Kọ ohun tí o rí sínú àkájọ ìwé, kí o sì fi ránṣẹ́ sí àwọn ìjọ méje tó wà ní: Éfésù,+ Símínà,+ Págámù,+ Tíátírà,+ Sádísì,+ Filadéfíà+ àti Laodíkíà.”+

12 Mo wẹ̀yìn kí n lè rí ẹni tó ń bá mi sọ̀rọ̀, nígbà tí mo sì wẹ̀yìn, mo rí ọ̀pá fìtílà méje tí wọ́n fi wúrà ṣe,+ 13 ẹnì kan tó dà bí ọmọ èèyàn+ wà láàárín àwọn ọ̀pá fìtílà náà, ó wọ aṣọ tó balẹ̀ dé ọrùn ẹsẹ̀, ó de ọ̀já wúrà mọ́ àyà rẹ̀. 14 Yàtọ̀ síyẹn, orí rẹ̀ àti irun rẹ̀ funfun bí ẹ̀gbọ̀n òwú, bíi yìnyín, ojú rẹ̀ sì dà bí ọwọ́ iná tó ń jó fòfò,+ 15 ẹsẹ̀ rẹ̀ dà bíi bàbà tó dáa gan-an+ tó ń tàn yòò nínú iná ìléru, ohùn rẹ̀ sì dà bí ìró omi tó pọ̀. 16 Ìràwọ̀ méje wà ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀,+ idà olójú méjì,+ tó mú, tó sì gùn yọ jáde láti ẹnu rẹ̀, ìrísí ojú rẹ̀ sì dà bí oòrùn tó ń mú ganrín-ganrín.+ 17 Nígbà tí mo rí i, mo ṣubú síbi ẹsẹ̀ rẹ̀ bíi pé mo ti kú.

Ó gbé ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ lé mi, ó sì sọ pé: “Má bẹ̀rù. Èmi ni Ẹni Àkọ́kọ́+ àti Ẹni Ìkẹyìn+ 18 àti alààyè,+ mo ti kú tẹ́lẹ̀,+ àmọ́ wò ó! mo wà láàyè títí láé àti láéláé,+ mo sì ní kọ́kọ́rọ́ ikú àti ti Isà Òkú.*+ 19 Torí náà, kọ àwọn ohun tí o rí sílẹ̀ àti àwọn ohun tó ń ṣẹlẹ̀ àti àwọn ohun tó máa ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn èyí. 20 Àṣírí mímọ́ ti ìràwọ̀ méje tí o rí ní ọwọ́ ọ̀tún mi àti ti ọ̀pá fìtílà méje tí wọ́n fi wúrà ṣe náà nìyí: Ìràwọ̀ méje náà túmọ̀ sí àwọn áńgẹ́lì ìjọ méje, ọ̀pá fìtílà méje náà sì túmọ̀ sí ìjọ méje.+

2 “Kọ̀wé sí áńgẹ́lì+ ìjọ ní Éfésù+ pé: Àwọn nǹkan tí ẹni tó di ìràwọ̀ méje mú ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ sọ nìyí, ẹni tó ń rìn láàárín ọ̀pá fìtílà méje tí wọ́n fi wúrà ṣe:+ 2 ‘Mo mọ àwọn iṣẹ́ rẹ àti làálàá tí ò ń ṣe àti ìfaradà rẹ, mo mọ̀ pé o ò jẹ́ gba àwọn èèyàn burúkú láyè àti pé o dán àwọn tó pe ara wọn ní àpọ́sítélì wò,+ àmọ́ tí wọn kì í ṣe àpọ́sítélì, o sì rí i pé òpùrọ́ ni wọ́n. 3 O tún fi hàn pé o ní ìfaradà, o ti mú ọ̀pọ̀ nǹkan mọ́ra nítorí orúkọ mi,+ àárẹ̀ ò sì mú ọ.+ 4 Síbẹ̀, ohun tí mo rí tí o ṣe tí kò dáa ni pé o ti fi ìfẹ́ tí o ní níbẹ̀rẹ̀ sílẹ̀.

5 “‘Torí náà, rántí ibi tí o ti ṣubú, kí o ronú pìwà dà,+ kí o sì ṣe àwọn iṣẹ́ tí o ṣe níbẹ̀rẹ̀. Tí o ò bá ṣe bẹ́ẹ̀, màá wá sọ́dọ̀ rẹ, màá sì gbé ọ̀pá fìtílà rẹ+ kúrò ní àyè rẹ̀, àfi tí o bá ronú pìwà dà.+ 6 Ohun míì tí o tún ṣe tó dáa ni pé: o kórìíra àwọn ohun tí ẹ̀ya ìsìn Níkóláósì+ ń ṣe, èmi náà sì kórìíra rẹ̀. 7 Kí ẹni tó bá ní etí gbọ́ ohun tí ẹ̀mí ń sọ fún àwọn ìjọ:+ Ẹni tó bá ṣẹ́gun+ ni màá jẹ́ kó jẹ nínú igi ìyè+ tó wà nínú párádísè Ọlọ́run.’

8 “Bákan náà, kọ̀wé sí áńgẹ́lì ìjọ ní Símínà pé: Àwọn nǹkan tí ‘Ẹni Àkọ́kọ́ àti Ẹni Ìkẹyìn’+ sọ nìyí, ẹni tó kú tẹ́lẹ̀, tó sì pa dà wà láàyè:+ 9 ‘Mo mọ ìpọ́njú àti ipò òṣì rẹ—àmọ́ ọlọ́rọ̀ ni ọ́+—àti ọ̀rọ̀ òdì àwọn tó ń pe ara wọn ní Júù, síbẹ̀ tí wọn kì í ṣe Júù, àmọ́ sínágọ́gù Sátánì ni wọ́n.+ 10 Má bẹ̀rù àwọn nǹkan tí o máa tó jìyà rẹ̀.+ Wò ó! Èṣù á máa ju àwọn kan nínú yín sí ẹ̀wọ̀n láti dán yín wò ní kíkún, ojú sì máa pọ́n yín fún ọjọ́ mẹ́wàá. Jẹ́ olóòótọ́, kódà títí dójú ikú, màá sì fún ọ ní adé ìyè.+ 11 Kí ẹni tó bá ní etí gbọ́  + ohun tí ẹ̀mí ń sọ fún àwọn ìjọ: Ó dájú pé ikú kejì+ kò ní pa ẹni tó bá ṣẹ́gun.’+

12 “Kọ̀wé sí áńgẹ́lì ìjọ ní Págámù pé: Àwọn nǹkan tí ẹni tó ní idà olójú méjì, tó mú, tó sì gùn+ sọ nìyí: 13 ‘Mo mọ ibi tí ò ń gbé, ìyẹn ibi tí ìtẹ́ Sátánì wà; síbẹ̀ ò ń di orúkọ mi mú ṣinṣin,+ o ò sì sẹ́ ìgbàgbọ́ rẹ nínú mi,+ kódà ní àwọn ọjọ́ Áńtípà, ẹlẹ́rìí mi tòótọ́,+ ẹni tí wọ́n pa+ ní ẹ̀gbẹ́ yín, níbi tí Sátánì ń gbé.

14 “‘Síbẹ̀, àwọn ohun kan wà tí mo rí tí ò ń ṣe tí kò dáa, àwọn kan wà láàárín yín tó ń tẹ̀ lé ẹ̀kọ́ Báláámù,+ ẹni tó kọ́ Bálákì+ pé kó fi ohun ìkọ̀sẹ̀ síwájú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, kí wọ́n jẹ àwọn ohun tí wọ́n fi rúbọ sí àwọn òrìṣà, kí wọ́n sì ṣe ìṣekúṣe.*+ 15 Bákan náà, àwọn tó ń tẹ̀ lé ẹ̀kọ́ ẹ̀ya ìsìn Níkóláósì tún wà láàárín yín.+ 16 Torí náà, ronú pìwà dà. Tí o ò bá ṣe bẹ́ẹ̀, màá wá sọ́dọ̀ rẹ ní kíákíá, màá sì fi idà gígùn ẹnu mi bá wọn jà.+

17 “‘Kí ẹni tó bá ní etí gbọ́ ohun tí ẹ̀mí ń sọ fún àwọn ìjọ:+ Màá fún ẹni tó bá ṣẹ́gun+ ní díẹ̀ nínú mánà tí a fi pa mọ́,+ màá sì fún un ní òkúta róbótó funfun kan, orúkọ tuntun kan sì máa wà lára òkúta róbótó náà, èyí tí ẹnì kankan ò mọ̀ àfi ẹni tó gbà á.’

18 “Kọ̀wé sí áńgẹ́lì ìjọ ní Tíátírà+ pé: Ohun tí Ọmọ Ọlọ́run sọ nìyí, ẹni tí ojú rẹ̀ dà bí ọwọ́ iná tó ń jó fòfò,+ tí ẹsẹ̀ rẹ̀ sì dà bíi bàbà tó dáa gan-an:+ 19 ‘Mo mọ àwọn iṣẹ́ rẹ àti ìfẹ́, ìgbàgbọ́, iṣẹ́ òjíṣẹ́ àti ìfaradà rẹ àti pé àwọn iṣẹ́ rẹ tí ò ń ṣe báyìí pọ̀ ju èyí tí o ṣe níbẹ̀rẹ̀.

20 “‘Síbẹ̀, àwọn ohun kan wà tí mo rí tí ò ń ṣe tí kò dáa, o fàyè gba Jésíbẹ́lì+ obìnrin yẹn, ẹni tó pe ara rẹ̀ ní wòlíì obìnrin, tó ń kọ́ àwọn ẹrú mi, tó sì ń ṣì wọ́n lọ́nà kí wọ́n lè ṣe ìṣekúṣe,*+ kí wọ́n sì jẹ àwọn nǹkan tí wọ́n fi rúbọ sí àwọn òrìṣà. 21 Mo ní sùúrù fún un kó lè ronú pìwà dà, àmọ́ kò fẹ́ ronú pìwà dà kúrò nínú ìṣekúṣe* rẹ̀. 22 Wò ó! Mo máa tó dá a dùbúlẹ̀ àìsàn, màá sì mú kí ìpọ́njú tó le gan-an bá àwọn tó ń bá a ṣe àgbèrè, àfi tí wọ́n bá ronú pìwà dà kúrò nínú àwọn iṣẹ́ rẹ̀. 23 Màá fi àjàkálẹ̀ àrùn pa àwọn ọmọ rẹ̀, kí gbogbo ìjọ lè mọ̀ pé èmi ni ẹni tó ń wá èrò inú* àti ọkàn, màá sì san án fún ẹnì kọ̀ọ̀kan yín bí iṣẹ́ yín bá ṣe rí.+

24 “‘Àmọ́, mo sọ fún ẹ̀yin yòókù ní Tíátírà, gbogbo ẹ̀yin tí ẹ ò tẹ̀ lé ẹ̀kọ́ yìí, ẹ̀yin tí ẹ ò mọ àwọn nǹkan tí wọ́n ń pè ní “àwọn ohun ìjìnlẹ̀ Sátánì”:+ Mi ò tún fi nǹkan míì ni yín lára. 25 Síbẹ̀, kí ẹ di ohun tí ẹ ní mú ṣinṣin títí mo fi máa dé.+ 26 Ẹni tó bá ṣẹ́gun, tó sì ń ṣe àwọn iṣẹ́ mi títí dé òpin ni màá fún ní àṣẹ lórí àwọn orílẹ̀-èdè,+ 27 ó sì máa fi ọ̀pá irin ṣe olùṣọ́ àgùntàn àwọn èèyàn,+ kó lè fọ́ wọn sí wẹ́wẹ́ bí ohun èlò tí wọ́n fi amọ̀ ṣe, bí mo ṣe gbà á lọ́wọ́ Baba mi gẹ́lẹ́. 28 Màá sì fún un ní ìràwọ̀ òwúrọ̀.+ 29 Kí ẹni tó bá ní etí gbọ́ ohun tí ẹ̀mí ń sọ fún àwọn ìjọ.’

3 “Kọ̀wé sí áńgẹ́lì ìjọ ní Sádísì pé: Àwọn ohun tí ẹni tó ní ẹ̀mí méje ti Ọlọ́run+ àti ìràwọ̀ méje+ sọ nìyí: ‘Mo mọ àwọn iṣẹ́ rẹ, pé o kàn ní orúkọ pé o wà láàyè* ni, àmọ́ o ti kú.+ 2 Máa ṣọ́ra,+ kí o sì fún àwọn ohun tó ṣẹ́ kù tó ti fẹ́rẹ̀ẹ́ kú lókun, torí mi ò tíì rí i kí o parí àwọn iṣẹ́ rẹ* níwájú Ọlọ́run mi. 3 Torí náà, máa fi bí o ṣe gbà àti bí o ṣe gbọ́ sọ́kàn,* kí o máa pa á mọ́, kí o sì ronú pìwà dà.+ Bí o ò bá jí, ó dájú pé màá wá bí olè,+ o ò sì ní mọ wákàtí tí màá dé bá ọ rárá.+

4 “‘Síbẹ̀, àwọn èèyàn díẹ̀ kan* wà ní Sádísì tí wọn ò sọ aṣọ wọn di ẹlẹ́gbin,+ a sì jọ máa rìn nínú aṣọ funfun,+ torí wọ́n yẹ. 5 Torí náà, ẹni tó bá ṣẹ́gun+ máa wọ aṣọ funfun,+ mi ò ní yọ orúkọ rẹ̀ kúrò* nínú ìwé ìyè,+ màá sì fi hàn pé mo mọ orúkọ rẹ̀ níwájú Baba mi àti níwájú àwọn áńgẹ́lì rẹ̀.+ 6 Kí ẹni tó bá ní etí gbọ́ ohun tí ẹ̀mí ń sọ fún àwọn ìjọ.’

7 “Kọ̀wé sí áńgẹ́lì ìjọ ní Filadéfíà pé: Àwọn ohun tí ẹni tó jẹ́ mímọ́+ sọ nìyí, ẹni tó jẹ́ òótọ́,+ tó ní kọ́kọ́rọ́ Dáfídì,+ ẹni tó ń ṣí, tí ẹnì kankan ò sì lè tì, tó sì ń tì, tí ẹnì kankan ò sì lè ṣí: 8 ‘Mo mọ àwọn iṣẹ́ rẹ—wò ó! mo ti ṣí ilẹ̀kùn sílẹ̀ níwájú rẹ,+ èyí tí ẹnì kankan ò lè tì. Mo mọ̀ pé agbára díẹ̀ lo ní, síbẹ̀ o pa ọ̀rọ̀ mi mọ́, o ò sì sẹ́ orúkọ mi. 9 Wò ó! Màá mú kí àwọn tó wá láti sínágọ́gù Sátánì, tí wọ́n ń pe ara wọn ní Júù, síbẹ̀ tí wọn kì í ṣe Júù,+ àmọ́ tí wọ́n ń parọ́—wò ó! màá mú kí wọ́n wá, kí wọ́n sì tẹrí ba* níwájú ẹsẹ̀ rẹ, màá sì jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé mo nífẹ̀ẹ́ rẹ. 10 Torí o pa ọ̀rọ̀ nípa ìfaradà mi mọ́,*+ màá pa ìwọ náà mọ́ nígbà wákàtí ìdánwò,+ èyí tó máa dé bá gbogbo ilẹ̀ ayé tí à ń gbé, láti dán àwọn tó ń gbé ayé wò. 11 Mò ń bọ̀ kíákíá.+ Di ohun tí o ní mú ṣinṣin, kí ẹnì kankan má bàa gba adé rẹ.+

12 “‘Màá fi ẹni tó bá ṣẹ́gun ṣe òpó nínú tẹ́ńpìlì Ọlọ́run mi, kò ní jáde kúrò nínú rẹ̀ mọ́, màá sì kọ orúkọ Ọlọ́run mi sára rẹ̀  + àti orúkọ ìlú Ọlọ́run mi, Jerúsálẹ́mù Tuntun+ tó ń sọ̀ kalẹ̀ bọ̀ láti ọ̀run látọ̀dọ̀ Ọlọ́run mi àti orúkọ mi tuntun.+ 13 Kí ẹni tó bá ní etí gbọ́ ohun tí ẹ̀mí ń sọ fún àwọn ìjọ.’

14 “Kọ̀wé sí áńgẹ́lì ìjọ ní Laodíkíà+ pé: Àwọn ohun tí Àmín+ sọ nìyí, ẹlẹ́rìí+ olóòótọ́ tó sì ṣeé gbára lé,+ ìbẹ̀rẹ̀ àwọn ohun tí Ọlọ́run dá:+ 15 ‘Mo mọ àwọn iṣẹ́ rẹ, pé o ò tutù, o ò sì gbóná. Ì bá wù mí kí o tutù tàbí kí o gbóná. 16 Àmọ́ torí pé ṣe lo lọ́wọ́ọ́wọ́, tí o ò gbóná,+ tí o ò sì tutù,+ màá pọ̀ ọ́ jáde lẹ́nu mi. 17 Torí o sọ pé, “Ọlọ́rọ̀ ni mí,+ mo ti kó ọrọ̀ jọ, mi ò sì nílò nǹkan kan,” àmọ́ o ò mọ̀ pé akúṣẹ̀ẹ́ ni ọ́, ẹni téèyàn ń káàánú, òtòṣì, afọ́jú àti ẹni tó wà ní ìhòòhò, 18 mo gbà ọ́ nímọ̀ràn pé kí o ra wúrà tí wọ́n fi iná yọ́ mọ́ lọ́dọ̀ mi, kí o lè di ọlọ́rọ̀, kí o ra aṣọ funfun kí o lè rí aṣọ wọ̀, kí ìtìjú má bàa bá ọ torí pé o wà ní ìhòòhò,+ kí o sì ra oògùn ojú láti fi pa ojú rẹ,+ kí o lè ríran.+

19 “‘Gbogbo àwọn tí mo fẹ́ràn ni mò ń bá wí, tí mo sì ń tọ́ sọ́nà.+ Torí náà, jẹ́ onítara, kí o sì ronú pìwà dà.+ 20 Wò ó! Mo dúró lẹ́nu ọ̀nà, mo sì ń kan ilẹ̀kùn. Tí ẹnikẹ́ni bá gbọ́ ohùn mi tó sì ṣí ilẹ̀kùn, màá wọ ilé rẹ̀, màá bá a jẹun alẹ́, òun náà á sì bá mi jẹun. 21 Màá jẹ́ kí ẹni tó bá ṣẹ́gun+ jókòó pẹ̀lú mi lórí ìtẹ́ mi,+ bí èmi náà ṣe ṣẹ́gun, tí mo sì jókòó+ pẹ̀lú Baba mi lórí ìtẹ́ rẹ̀. 22 Kí ẹni tó bá ní etí gbọ́ ohun tí ẹ̀mí ń sọ fún àwọn ìjọ.’”

4 Lẹ́yìn èyí, wò ó! mo rí ilẹ̀kùn kan tó ṣí sílẹ̀ ní ọ̀run, ohùn tí mo sì kọ́kọ́ gbọ́ tó ń bá mi sọ̀rọ̀ dún bíi kàkàkí, ó sọ pé: “Máa bọ̀ lókè níbí, màá sì fi àwọn ohun tó gbọ́dọ̀ ṣẹlẹ̀ hàn ọ́.” 2 Lẹ́yìn èyí, mo wà nínú agbára ẹ̀mí lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, sì wò ó! ìtẹ́ kan wà ní àyè rẹ̀ ní ọ̀run, ẹnì kan sì jókòó sórí ìtẹ́ náà.+ 3 Ẹni tó jókòó sórí ìtẹ́ náà rí bí òkúta jásípérì+ àti òkúta sádísì,* òṣùmàrè kan tó dà bí òkúta émírádì sì wà yí ká ìtẹ́ náà.+

4 Ìtẹ́ mẹ́rìnlélógún (24) wà yí ká ìtẹ́ náà, mo rí àwọn àgbààgbà mẹ́rìnlélógún (24)+ tí wọ́n wọ aṣọ funfun, wọ́n jókòó sórí àwọn ìtẹ́ náà, wọ́n sì dé adé wúrà. 5 Mànàmáná+ àti ohùn àti ààrá+ sì ń jáde wá láti ibi ìtẹ́ náà; fìtílà méje tó ní iná ń jó níwájú ìtẹ́ náà, àwọn yìí sì túmọ̀ sí ẹ̀mí méje ti Ọlọ́run.+ 6 Ohun kan tó rí bí òkun tó ń dán bíi gíláàsì+ wà níwájú ìtẹ́ náà, ó dà bíi kírísítálì.

Ẹ̀dá alààyè mẹ́rin+ tí ojú kún iwájú àti ẹ̀yìn wọn wà ní àárín ìtẹ́ náà* àti yí ká ìtẹ́ náà. 7 Ẹ̀dá alààyè àkọ́kọ́ dà bíi kìnnìún,+ ẹ̀dá alààyè kejì dà bí akọ ọmọ màlúù,+ ẹ̀dá alààyè kẹta+ ní ojú bíi ti èèyàn, ẹ̀dá alààyè kẹrin+ sì dà bí ẹyẹ idì tó ń fò.+ 8 Ní ti àwọn ẹ̀dá alààyè mẹ́rin náà, ọ̀kọ̀ọ̀kan ní ìyẹ́ mẹ́fà tí ojú kún ara rẹ̀ yí ká àti lábẹ́.+ Tọ̀sántòru ni wọ́n ń sọ pé: “Mímọ́, mímọ́, mímọ́ ni Jèhófà*+ Ọlọ́run, Olódùmarè, tó ti wà tipẹ́, tó wà báyìí, tó sì ń bọ̀.”+

9 Nígbàkigbà tí àwọn ẹ̀dá alààyè náà bá fi ògo àti ọlá fún Ẹni tó jókòó lórí ìtẹ́, Ẹni tó wà láàyè títí láé àti láéláé,+ tí wọ́n sì dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀, 10 àwọn àgbààgbà mẹ́rìnlélógún (24) náà+ á wólẹ̀ níwájú Ẹni tó jókòó lórí ìtẹ́, wọ́n á jọ́sìn Ẹni tó wà láàyè títí láé àti láéláé, wọ́n á sì fi adé wọn lélẹ̀ níwájú ìtẹ́ náà, wọ́n á sọ pé: 11 “Jèhófà,* Ọlọ́run wa, ìwọ ló tọ́ sí láti gba ògo+ àti ọlá+ àti agbára,+ torí ìwọ lo dá ohun gbogbo,+ torí ìfẹ́ rẹ ni wọ́n ṣe wà, tí a sì dá wọn.”

5 Mo sì rí àkájọ ìwé kan lọ́wọ́ ọ̀tún Ẹni tó jókòó lórí ìtẹ́ náà,+ tí wọ́n kọ̀wé sí tojú tẹ̀yìn,* tí wọ́n sì fi èdìdì méje dì pinpin. 2 Mo sì rí áńgẹ́lì alágbára kan tó ń fi ohùn tó rinlẹ̀ kéde pé: “Ta ló yẹ kó ṣí àkájọ ìwé náà, kó sì tú àwọn èdìdì rẹ̀?” 3 Àmọ́ kò sí ẹnikẹ́ni ní ọ̀run tàbí ní ayé tàbí lábẹ́ ilẹ̀ tó lè ṣí àkájọ ìwé náà tàbí wo inú rẹ̀. 4 Mo bẹ̀rẹ̀ sí í sunkún gidigidi torí a ò rí ẹnì kankan tó yẹ láti ṣí àkájọ ìwé náà tàbí wo inú rẹ̀. 5 Àmọ́ ọ̀kan lára àwọn àgbààgbà náà sọ fún mi pé: “Má sunkún mọ́. Wò ó! Kìnnìún ẹ̀yà Júdà,+ gbòǹgbò+ Dáfídì,+ ti ṣẹ́gun+ kó lè ṣí àkájọ ìwé náà àti èdìdì méje rẹ̀.”

6 Mo sì rí ọ̀dọ́ àgùntàn+ kan tó rí bí èyí tí wọ́n ti pa,+ ó dúró ní àárín ìtẹ́ náà àti àwọn ẹ̀dá alààyè mẹ́rin náà àti ní àárín àwọn àgbààgbà náà,+ ó ní ìwo méje àti ojú méje, àwọn ojú náà sì túmọ̀ sí ẹ̀mí méje ti Ọlọ́run+ tí a ti rán jáde sí gbogbo ayé. 7 Ó wá síwájú lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, ó sì gba àkájọ ìwé náà lọ́wọ́ ọ̀tún Ẹni tó jókòó lórí ìtẹ́.+ 8 Nígbà tó gbà á, àwọn ẹ̀dá alààyè mẹ́rin àti àwọn àgbààgbà mẹ́rìnlélógún  + (24) náà wólẹ̀ níwájú Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà, ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn ní háàpù kan lọ́wọ́ àti abọ́ wúrà tí tùràrí kún inú rẹ̀. (Tùràrí náà túmọ̀ sí àdúrà àwọn ẹni mímọ́.)+ 9 Wọ́n sì ń kọ orin tuntun+ kan pé: “Ìwọ ló yẹ kó gba àkájọ ìwé náà, kí o sì ṣí àwọn èdìdì rẹ̀, torí pé wọ́n pa ọ́, o sì fi ẹ̀jẹ̀ rẹ ra àwọn èèyàn fún Ọlọ́run+ látinú gbogbo ẹ̀yà àti ahọ́n* àti èèyàn àti orílẹ̀-èdè,+ 10 o mú kí wọ́n di ìjọba kan+ àti àlùfáà fún Ọlọ́run wa,+ wọ́n sì máa ṣàkóso bí ọba+ lé ayé lórí.”

11 Mo rí ọ̀pọ̀ áńgẹ́lì, mo sì gbọ́ ohùn wọn, wọ́n wà yí ká ìtẹ́ náà àti àwọn ẹ̀dá alààyè àti àwọn àgbààgbà náà, iye wọn jẹ́ ẹgbẹẹgbàárùn-ún lọ́nà ẹgbẹẹgbàárùn-ún* àti ẹgbẹẹgbẹ̀rún lọ́nà ẹgbẹẹgbẹ̀rún,+ 12 wọ́n ń ké jáde pé: “Ọ̀dọ́ Àgùntàn tí wọ́n pa+ ló yẹ láti gba agbára àti ọrọ̀ àti ọgbọ́n àti okun àti ọlá àti ògo àti ìbùkún.”+

13 Mo gbọ́ tí gbogbo ẹ̀dá tó wà ní ọ̀run àti ayé àti lábẹ́ ilẹ̀+ àti lórí òkun àti gbogbo ohun tó wà nínú wọn, ń sọ pé: “Kí ìbùkún àti ọlá+ àti ògo àti agbára jẹ́ ti Ẹni tó jókòó sórí ìtẹ́ náà+ àti Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà+ títí láé àti láéláé.”+ 14 Àwọn ẹ̀dá alààyè mẹ́rin náà ń sọ pé: “Àmín!” àwọn àgbààgbà náà wólẹ̀, wọ́n sì jọ́sìn.

6 Mo rí Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà+ nígbà tó ṣí ọ̀kan nínú àwọn èdìdì méje náà,+ mo sì gbọ́ tí ọ̀kan nínú àwọn ẹ̀dá alààyè mẹ́rin náà+ fi ohùn tó dún bí ààrá sọ pé: “Máa bọ̀!” 2 Sì wò ó! mo rí ẹṣin funfun kan,+ ẹni tó jókòó sórí rẹ̀ ní ọfà* kan; a sì fún un ní adé,+ ó jáde lọ, ó ń ṣẹ́gun, kó lè parí ìṣẹ́gun rẹ̀.+

3 Nígbà tó ṣí èdìdì kejì, mo gbọ́ tí ẹ̀dá alààyè kejì+ sọ pé: “Máa bọ̀!” 4 Ẹṣin míì jáde wá, ó jẹ́ aláwọ̀ iná, a sì gba ẹni tó jókòó sórí rẹ̀ láyè láti mú àlàáfíà kúrò ní ayé kí wọ́n lè máa pa ara wọn, a sì fún un ní idà ńlá kan.+

5 Nígbà tó ṣí èdìdì kẹta,+ mo gbọ́ tí ẹ̀dá alààyè kẹta+ sọ pé: “Máa bọ̀!” Sì wò ó! mo rí ẹṣin dúdú kan, òṣùwọ̀n aláwẹ́ méjì sì wà lọ́wọ́ ẹni tó jókòó sórí rẹ̀. 6 Mo gbọ́ tí nǹkan kan dún bí ohùn láàárín àwọn ẹ̀dá alààyè mẹ́rin náà, ó sọ pé: “Òṣùwọ̀n kúọ̀tì* àlìkámà* kan fún owó dínárì*+ kan àti òṣùwọ̀n kúọ̀tì mẹ́ta ọkà báálì fún owó dínárì kan; má sì pa òróró ólífì àti wáìnì lára.”+

7 Nígbà tó ṣí èdìdì kẹrin, mo gbọ́ ohùn ẹ̀dá alààyè kẹrin,+ ó sọ pé: “Máa bọ̀!” 8 Sì wò ó! mo rí ẹṣin ràndánràndán kan, Ikú ni orúkọ ẹni tó jókòó sórí rẹ̀. Isà Òkú* sì ń tẹ̀ lé e pẹ́kípẹ́kí. A sì fún wọn ní àṣẹ lórí ìdá mẹ́rin ayé pé kí wọ́n fi idà gígùn, ìyàn,+ àjàkálẹ̀ àrùn àti àwọn ẹran inú igbó pani.+

9 Nígbà tó ṣí èdìdì karùn-ún, mo rí ọkàn*+ àwọn kan lábẹ́ pẹpẹ,+ àwọn tí wọ́n pa torí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run àti torí ẹ̀rí tí wọ́n jẹ́.+ 10 Wọ́n ké jáde pé: “Olúwa Ọba Aláṣẹ, ẹni mímọ́ àti olóòótọ́,+ títí di ìgbà wo lo fi máa dúró kí o tó ṣe ìdájọ́, kí o sì gbẹ̀san ẹ̀jẹ̀ wa lára àwọn tó ń gbé ayé?”+ 11 A fún ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn ní aṣọ funfun kan,+ a sì sọ fún wọn pé kí wọ́n sinmi fúngbà díẹ̀ sí i, títí iye àwọn ẹrú bíi tiwọn àti àwọn arákùnrin wọn tí wọ́n máa tó pa bí wọ́n ṣe pa àwọn náà fi máa pé.+

12 Mo sì rí i nígbà tó ṣí èdìdì kẹfà, ìmìtìtì ilẹ̀ tó lágbára ṣẹlẹ̀; oòrùn di dúdú bí aṣọ ọ̀fọ̀* tí a fi irun* ṣe, gbogbo òṣùpá dà bí ẹ̀jẹ̀,+ 13 àwọn ìràwọ̀ ọ̀run sì já bọ́ sí ayé, bí ìgbà tí atẹ́gùn líle mú kí èso igi ọ̀pọ̀tọ́ tí kò tíì pọ́n já bọ́. 14 Ọ̀run sì lọ bí àkájọ ìwé tí wọ́n ká,+ a sì mú kí gbogbo òkè àti gbogbo erékùṣù kúrò ní àyè wọn.+ 15 Lẹ́yìn náà, àwọn ọba ayé, àwọn aláṣẹ, àwọn ọ̀gágun, àwọn ọlọ́rọ̀, àwọn alágbára, gbogbo ẹrú àti gbogbo àwọn tó wà lómìnira fi ara wọn pa mọ́ sínú àwọn ihò àti sáàárín àwọn àpáta àwọn òkè.+ 16 Wọ́n sì ń sọ fún àwọn àpáta àti àwọn òkè náà pé: “Ẹ wó lù wá,+ kí ẹ sì fi wá pa mọ́ kúrò lójú Ẹni tó jókòó sórí ìtẹ́+ àti kúrò lọ́wọ́ ìbínú Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà,+ 17 torí ọjọ́ ńlá ìbínú wọn ti dé,+ ta ló sì lè dúró?”+

7 Lẹ́yìn èyí, mo rí áńgẹ́lì mẹ́rin tí wọ́n dúró lórí igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ayé, wọ́n di atẹ́gùn mẹ́rin ayé mú pinpin, kí atẹ́gùn kankan má bàa fẹ́ sórí ayé tàbí sórí òkun tàbí sórí igi èyíkéyìí. 2 Mo rí áńgẹ́lì míì tó ń gòkè láti ibi tí oòrùn ti ń yọ,* ó ní èdìdì Ọlọ́run alààyè; ó sì ké jáde sí àwọn áńgẹ́lì mẹ́rin tí a gbà láyè kí wọ́n pa ayé àti òkun lára, 3 ó sọ pé: “Ẹ má ṣe pa ayé tàbí òkun tàbí àwọn igi lára, títí a fi máa gbé èdìdì lé+ iwájú orí+ àwọn ẹrú Ọlọ́run wa.”

4 Mo sì gbọ́ iye àwọn tí a gbé èdìdì lé, ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì+ (144,000), a gbé èdìdì lé wọn látinú gbogbo ẹ̀yà àwọn ọmọ Ísírẹ́lì:+

5 Látinú ẹ̀yà Júdà, a gbé èdìdì lé ẹgbẹ̀rún méjìlá (12,000);

látinú ẹ̀yà Rúbẹ́nì, ẹgbẹ̀rún méjìlá (12,000);

látinú ẹ̀yà Gádì, ẹgbẹ̀rún méjìlá (12,000);

6 látinú ẹ̀yà Áṣérì, ẹgbẹ̀rún méjìlá (12,000);

látinú ẹ̀yà Náfútálì, ẹgbẹ̀rún méjìlá (12,000);

látinú ẹ̀yà Mánásè,+ ẹgbẹ̀rún méjìlá (12,000);

7 látinú ẹ̀yà Síméónì, ẹgbẹ̀rún méjìlá (12,000);

látinú ẹ̀yà Léfì, ẹgbẹ̀rún méjìlá (12,000);

látinú ẹ̀yà Ísákà, ẹgbẹ̀rún méjìlá (12,000);

8 látinú ẹ̀yà Sébúlúnì, ẹgbẹ̀rún méjìlá (12,000);

látinú ẹ̀yà Jósẹ́fù, ẹgbẹ̀rún méjìlá (12,000);

látinú ẹ̀yà Bẹ́ńjámínì, a gbé èdìdì lé ẹgbẹ̀rún méjìlá (12,000).

9 Lẹ́yìn èyí, wò ó! mo rí ogunlọ́gọ̀ èèyàn,* tí èèyàn kankan kò lè ka iye wọn, wọ́n wá látinú gbogbo orílẹ̀-èdè àti ẹ̀yà àti èèyàn àti ahọ́n,*+ wọ́n dúró níwájú ìtẹ́ àti níwájú Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà, wọ́n wọ aṣọ funfun;+ imọ̀ ọ̀pẹ sì wà lọ́wọ́ wọn.+ 10 Wọ́n ń ké jáde pé: “Ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wa tó jókòó sórí ìtẹ́+ àti Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà ni ìgbàlà wa ti wá.”+

11 Gbogbo àwọn áńgẹ́lì dúró yí ká ìtẹ́ náà àti àwọn àgbààgbà náà+ àti àwọn ẹ̀dá alààyè mẹ́rin náà, wọ́n dojú bolẹ̀ níwájú ìtẹ́ náà, wọ́n sì jọ́sìn Ọlọ́run, 12 wọ́n ń sọ pé: “Àmín! Kí ìyìn àti ògo àti ọgbọ́n àti ọpẹ́ àti ọlá àti agbára àti okun jẹ́ ti Ọlọ́run wa títí láé àti láéláé.+ Àmín.”

13 Ọ̀kan nínú àwọn àgbààgbà náà dáhùn, ó bi mí pé: “Àwọn wo ni àwọn tó wọ aṣọ funfun yìí,+ ibo ni wọ́n sì ti wá?” 14 Mo sọ fún un lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ pé: “Olúwa mi, ìwọ lo mọ̀ ọ́n.” Ó wá sọ fún mi pé: “Àwọn yìí ni àwọn tó wá látinú ìpọ́njú ńlá náà,+ wọ́n ti fọ aṣọ wọn, wọ́n sì ti sọ wọ́n di funfun nínú ẹ̀jẹ̀ Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà.+ 15 Ìdí nìyẹn tí wọ́n fi wà níwájú ìtẹ́ Ọlọ́run, wọ́n ń ṣe iṣẹ́ ìsìn mímọ́ fún un tọ̀sántòru nínú tẹ́ńpìlì rẹ̀; Ẹni tó jókòó lórí ìtẹ́+ sì máa fi àgọ́ rẹ̀ bò wọ́n.+ 16 Ebi ò ní pa wọ́n mọ́, òùngbẹ ò sì ní gbẹ wọ́n mọ́, bẹ́ẹ̀ ni oòrùn ò ní pa wọ́n, ooru èyíkéyìí tó ń jóni ò sì ní mú wọn,+ 17 torí Ọ̀dọ́ Àgùntàn,+ tó wà ní àárín ìtẹ́ náà, máa ṣe olùṣọ́ àgùntàn wọn,+ ó sì máa darí wọn lọ sí àwọn ìsun* omi ìyè.+ Ọlọ́run sì máa nu gbogbo omijé kúrò ní ojú wọn.”+

8 Nígbà tó+ ṣí èdìdì keje,+ gbogbo ọ̀run pa rọ́rọ́ fún nǹkan bí ààbọ̀ wákàtí. 2 Mo sì rí àwọn áńgẹ́lì méje+ tí wọ́n dúró níwájú Ọlọ́run, a fún wọn ní kàkàkí méje.

3 Áńgẹ́lì míì dé, ó dúró níbi pẹpẹ,+ ó gbé àwo tùràrí tí wọ́n fi wúrà ṣe* dání, a sì fún un ní tùràrí tó pọ̀ gan-an+ pé kó sun ún lórí pẹpẹ tí wọ́n fi wúrà ṣe+ tó wà níwájú ìtẹ́ náà bí gbogbo àwọn ẹni mímọ́ ṣe ń gbàdúrà. 4 Èéfín tùràrí látọwọ́ áńgẹ́lì náà àti àdúrà+ àwọn ẹni mímọ́ gòkè lọ síwájú Ọlọ́run. 5 Àmọ́ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, áńgẹ́lì náà mú àwo tùràrí náà, ó kó díẹ̀ lára iná pẹpẹ sínú rẹ̀, ó sì jù ú sí ayé. Ààrá sán, a gbọ́ ohùn, mànàmáná kọ yẹ̀rì,+ ìmìtìtì ilẹ̀ sì wáyé. 6 Àwọn áńgẹ́lì méje tí kàkàkí méje wà lọ́wọ́ wọn+ sì múra láti fun wọ́n.

7 Áńgẹ́lì àkọ́kọ́ fun kàkàkí rẹ̀. Yìnyín àti iná dà pọ̀ mọ́ ẹ̀jẹ̀, a sì dà á sí ayé;  + ìdá mẹ́ta ayé sì jóná àti ìdá mẹ́ta àwọn igi pẹ̀lú gbogbo ewéko tútù.+

8 Áńgẹ́lì kejì fun kàkàkí rẹ̀. A sì ju ohun kan tó rí bí òkè ńlá tí iná ń jó sínú òkun.+ Ìdá mẹ́ta òkun di ẹ̀jẹ̀;+ 9 ìdá mẹ́ta àwọn ohun alààyè* tó wà nínú òkun sì kú,+ ìdá mẹ́ta àwọn ọkọ̀ òkun sì fọ́ túútúú.

10 Áńgẹ́lì kẹta fun kàkàkí rẹ̀. Ìràwọ̀ ńlá tó ń jó bíi fìtílà já bọ́ láti ọ̀run, ó já bọ́ sórí ìdá mẹ́ta àwọn odò àti sórí àwọn ìsun omi.*+ 11 Iwọ* ni orúkọ ìràwọ̀ náà. Ìdá mẹ́ta àwọn omi di iwọ, àwọn omi náà sì pa ọ̀pọ̀ èèyàn, torí a ti mú kí wọ́n korò.+

12 Áńgẹ́lì kẹrin fun kàkàkí rẹ̀. A sì lu ìdá mẹ́ta oòrùn+ àti ìdá mẹ́ta òṣùpá àti ìdá mẹ́ta àwọn ìràwọ̀, kí òkùnkùn lè bo ìdá mẹ́ta wọn,+ kí ìmọ́lẹ̀ má bàa wà ní ìdá mẹ́ta ọ̀sán àti òru pẹ̀lú.

13 Mo rí ẹyẹ idì kan tó ń fò lójú ọ̀run, mo sì gbọ́ tó ń ké jáde pé: “Ẹ gbé, ẹ gbé, ẹ gbé+ ẹ̀yin tí ẹ̀ ń gbé ní ayé nítorí ìró kàkàkí àwọn áńgẹ́lì mẹ́ta yòókù tí wọ́n máa tó fun kàkàkí wọn!”+

9 Áńgẹ́lì karùn-ún fun kàkàkí rẹ̀.+ Mo sì rí ìràwọ̀ kan tó ti já bọ́ láti ọ̀run sí ayé, a sì fún un ní kọ́kọ́rọ́ àbáwọlé* ọ̀gbun àìnísàlẹ̀.+ 2 Ó ṣí àbáwọlé* ọ̀gbun àìnísàlẹ̀ náà, èéfín sì jáde látinú ọ̀gbun náà bí èéfín iná ìléru ńlá, èéfín tó ń jáde látinú ọ̀gbun náà sì mú kí oòrùn ṣókùnkùn+ bẹ́ẹ̀ náà sì ni afẹ́fẹ́. 3 Àwọn eéṣú wá jáde sí ayé látinú èéfín náà,+ a sì fún wọn ní àṣẹ, àṣẹ kan náà tí àwọn àkekèé tó wà ní ayé ní. 4 A sọ fún wọn pé kí wọ́n má pa koríko ayé lára tàbí ewéko tútù tàbí igi èyíkéyìí, àwọn èèyàn tí kò ní èdìdì Ọlọ́run ní iwájú orí wọn nìkan ni kí wọ́n pa lára.+

5 A ò gbà kí àwọn eéṣú náà pa wọ́n, àmọ́ kí wọ́n dá wọn lóró fún oṣù márùn-ún, oró wọn sì dà bí ìgbà tí àkekèé+ bá ta èèyàn. 6 Ní àwọn ọjọ́ yẹn, àwọn èèyàn máa wá ikú, àmọ́ wọn ò ní rí i rárá, wọ́n máa fẹ́ kú, ṣùgbọ́n ikú máa sá fún wọn.

7 Àwọn eéṣú náà rí bí àwọn ẹṣin tó ṣe tán láti jagun;+ ohun tó dà bí adé tí wọ́n fi wúrà ṣe wà ní orí wọn, ojú wọn sì dà bíi ti èèyàn, 8 àmọ́ wọ́n ní irun bíi ti obìnrin. Eyín wọn sì dà bíi ti kìnnìún,+ 9 wọ́n sì ní ìgbàyà tó dà bí èyí tí wọ́n fi irin ṣe. Ìró ìyẹ́ wọn sì dà bí ìró àwọn kẹ̀kẹ́ ẹṣin tó ń sáré lọ sójú ogun.+ 10 Bákan náà, wọ́n ní ìrù tó lè tani bíi ti àkekèé, àṣẹ sì wà ní ìrù wọn láti ṣe àwọn èèyàn náà léṣe fún oṣù márùn-ún.+ 11 Wọ́n ní ẹni tó ń jọba lé wọn lórí, áńgẹ́lì ọ̀gbun àìnísàlẹ̀.+ Orúkọ rẹ̀ lédè Hébérù ni Ábádónì,* àmọ́ lédè Gíríìkì orúkọ rẹ̀ ni Ápólíónì.*

12 Ìyọnu àkọ́kọ́ ti kọjá. Wò ó! Ìyọnu méjì míì+ ń bọ̀ lẹ́yìn àwọn nǹkan yìí.

13 Áńgẹ́lì kẹfà+ fun kàkàkí rẹ̀.+ Mo sì gbọ́ ohùn kan, ó wá látinú àwọn ìwo tó wà lórí pẹpẹ, èyí tí wọ́n fi wúrà ṣe+ tó wà níwájú Ọlọ́run, 14 ó sọ fún áńgẹ́lì kẹfà tó mú kàkàkí dání pé: “Tú àwọn áńgẹ́lì mẹ́rin tí wọ́n dè síbi odò ńlá Yúfírétì+ sílẹ̀.” 15 A sì tú àwọn áńgẹ́lì mẹ́rin náà sílẹ̀, àwọn tí a ti múra sílẹ̀ fún wákàtí àti ọjọ́ àti oṣù àti ọdún náà, kí wọ́n lè pa ìdá mẹ́ta àwọn èèyàn náà.

16 Iye àwọn ọmọ ogun tó gẹṣin jẹ́ ẹgbàárùn-ún méjì lọ́nà ẹgbàárùn-ún;* mo gbọ́ iye wọn. 17 Báyìí sì ni àwọn ẹṣin tí mo rí nínú ìran náà àti àwọn tó jókòó sórí wọn ṣe rí: Wọ́n ní ìgbàyà tó pupa bí iná àti búlúù bíi háyásíǹtì àti yẹ́lò bí imí ọjọ́, orí àwọn ẹṣin náà sì dà bí orí kìnnìún,+ iná, èéfín àti imí ọjọ́ sì jáde láti ẹnu wọn. 18 Ìyọnu mẹ́ta yìí, ìyẹn iná, èéfín àti imí ọjọ́ tó jáde lẹ́nu wọn, pa ìdá mẹ́ta àwọn èèyàn náà. 19 Torí àṣẹ àwọn ẹṣin náà wà ní ẹnu wọn àti ìrù wọn, nítorí ìrù wọn dà bí ejò, wọ́n sì ní orí, àwọn nǹkan yìí ni wọ́n fi ń ṣe àwọn èèyàn léṣe.

20 Àmọ́ àwọn èèyàn yòókù tí àwọn ìyọnu yìí kò pa kò ronú pìwà dà iṣẹ́ ọwọ́ wọn; wọn ò ṣíwọ́ láti máa jọ́sìn àwọn ẹ̀mí èṣù àti àwọn òrìṣà tí wọ́n fi wúrà àti fàdákà àti bàbà àti òkúta àti igi ṣe, tí kò lè ríran, tí kò lè gbọ́ràn, tí kò sì lè rìn.+ 21 Wọn ò sì ronú pìwà dà nínú ìpànìyàn, ìbẹ́mìílò, ìṣekúṣe* tàbí olè jíjà wọn.

10 Mo rí áńgẹ́lì alágbára míì tó ń sọ̀ kalẹ̀ láti ọ̀run, tí a fi ìkùukùu* ṣe ní ọ̀ṣọ́,* òṣùmàrè wà ní orí rẹ̀, ojú rẹ̀ dà bí oòrùn,+ ẹsẹ̀* rẹ̀ dà bí ọwọ̀n iná, 2 àkájọ ìwé kékeré kan tí a ṣí sílẹ̀ sì wà ní ọwọ́ rẹ̀. Ó gbé ẹsẹ̀ rẹ̀ ọ̀tún sórí òkun, àmọ́ ó gbé ẹsẹ̀ rẹ̀ òsì sórí ilẹ̀, 3 ó sì ké jáde bí ìgbà tí kìnnìún bá ké ramúramù.+ Nígbà tó ké jáde, ààrá méje+ sọ̀rọ̀.

4 Nígbà tí ààrá méje náà sọ̀rọ̀, mo fẹ́ kọ̀wé, àmọ́ mo gbọ́ ohùn kan láti ọ̀run+ tó sọ pé: “Gbé èdìdì lé àwọn ohun tí ààrá méje náà sọ, má sì kọ wọ́n sílẹ̀.” 5 Áńgẹ́lì tí mo rí tó dúró sórí òkun àti ilẹ̀ na ọwọ́ rẹ̀ ọ̀tún sókè ọ̀run, 6 ó sì fi Ẹni tó wà láàyè títí láé àti láéláé+ búra, ẹni tó dá ọ̀run àti àwọn ohun tó wà nínú rẹ̀, ayé àti àwọn ohun tó wà nínú rẹ̀, pẹ̀lú òkun àti àwọn ohun tó wà nínú rẹ̀,+ ó sọ pé: “A ò ní fi falẹ̀ mọ́. 7 Àmọ́ ní àwọn ọjọ́ tí áńgẹ́lì keje+ ti fẹ́ fun kàkàkí rẹ̀,+ àṣírí mímọ́  + tí Ọlọ́run kéde pé ó jẹ́ ìròyìn ayọ̀ fún àwọn ẹrú rẹ̀ tí wọ́n jẹ́ wòlíì+ wá sí òpin ní tòótọ́.”

8 Mo sì gbọ́ ohùn láti ọ̀run+ tó tún ń bá mi sọ̀rọ̀, ó sọ pé: “Lọ, kí o gba àkájọ ìwé tí a ṣí sílẹ̀ tó wà ní ọwọ́ áńgẹ́lì tó dúró lórí òkun àti ilẹ̀.”+ 9 Mo lọ bá áńgẹ́lì náà, mo sì sọ fún un pé kó fún mi ní àkájọ ìwé kékeré náà. Ó sọ fún mi pé: “Gbà, kí o jẹ ẹ́ tán,+ ó máa mú kí ikùn rẹ korò, àmọ́ ó máa dùn bí oyin ní ẹnu rẹ.” 10 Mo gba àkájọ ìwé kékeré náà ní ọwọ́ áńgẹ́lì náà, mo sì jẹ ẹ́,+ ó dùn bí oyin ní ẹnu mi,+ àmọ́ nígbà tí mo jẹ ẹ́ tán, ó mú kí ikùn mi korò. 11 Wọ́n sì sọ fún mi pé: “O gbọ́dọ̀ tún sọ tẹ́lẹ̀ nípa àwọn èèyàn àti àwọn orílẹ̀-èdè àti àwọn ahọ́n* àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọba.”

11 A sì fún mi ní esùsú* kan tó dà bí ọ̀pá*+ bó ṣe ń sọ pé: “Dìde, kí o wọn ibi mímọ́ tẹ́ńpìlì Ọlọ́run àti pẹpẹ àti àwọn tó ń jọ́sìn nínú rẹ̀. 2 Àmọ́ ní ti àgbàlá tó wà ní ìta ibi mímọ́ tẹ́ńpìlì, fi sílẹ̀, má sì wọ̀n ọ́n, torí a ti fún àwọn orílẹ̀-èdè, wọ́n sì máa fi ẹsẹ̀ wọn tẹ ìlú mímọ́ náà+ mọ́lẹ̀ fún oṣù méjìlélógójì+ (42). 3 Màá mú kí àwọn ẹlẹ́rìí mi méjì fi ọ̀tàlélẹ́gbẹ̀fà ọjọ́ (1,260) sọ tẹ́lẹ̀, wọ́n á sì wọ aṣọ ọ̀fọ̀.”* 4 Àwọn yìí ni igi ólífì méjì+ àti ọ̀pá fìtílà méjì ṣàpẹẹrẹ,+ wọ́n dúró síwájú Olúwa ilẹ̀ ayé.+

5 Tí ẹnikẹ́ni bá fẹ́ pa wọ́n lára, iná á jáde láti ẹnu wọn, á sì jó àwọn ọ̀tá wọn run. Bí a ṣe máa pa ẹnikẹ́ni tó bá fẹ́ pa wọ́n lára nìyí. 6 Àwọn yìí ní àṣẹ láti sé òfúrufú* pa+ kí òjò kankan má bàa rọ̀+ ní àwọn ọjọ́ tí wọ́n ń sọ tẹ́lẹ̀, wọ́n sì ní àṣẹ lórí àwọn omi láti sọ wọ́n di ẹ̀jẹ̀+ àti láti fi gbogbo oríṣiríṣi ìyọnu kọ lu ayé ní gbogbo ìgbà tí wọ́n bá fẹ́.

7 Nígbà tí wọ́n bá jẹ́rìí tán, ẹranko tó jáde látinú ọ̀gbun àìnísàlẹ̀ máa bá wọn jagun, ó máa ṣẹ́gun wọn, ó sì máa pa wọ́n.+ 8 Òkú wọn sì máa wà lójú ọ̀nà ìlú ńlá náà, èyí tí wọ́n ń pè ní Sódómù àti Íjíbítì lọ́nà ti ẹ̀mí, níbi tí wọ́n ti kan Olúwa wọn pẹ̀lú mọ́gi. 9 Àwọn kan látinú àwọn èèyàn àti àwọn ẹ̀yà àti àwọn ahọ́n* àti àwọn orílẹ̀-èdè máa fi ọjọ́ mẹ́ta àti ààbọ̀+ wo òkú wọn, wọn ò sì ní jẹ́ kí wọ́n tẹ́ òkú wọn sínú ibojì. 10 Àwọn tó ń gbé ní ayé yọ̀ torí wọn, wọ́n ṣe àjọyọ̀, wọ́n sì máa fi àwọn ẹ̀bùn ránṣẹ́ sí ara wọn, torí pé àwọn wòlíì méjì yìí ti dá àwọn tó ń gbé ayé lóró.

11 Lẹ́yìn ọjọ́ mẹ́ta àti ààbọ̀ náà, ẹ̀mí ìyè látọ̀dọ̀ Ọlọ́run wọnú wọn,+ wọ́n dúró lórí ẹsẹ̀ wọn, ẹ̀rù sì ba àwọn tó rí wọn gidigidi. 12 Wọ́n wá gbọ́ ohùn kan tó ké jáde sí wọn láti ọ̀run pé: “Ẹ máa bọ̀ lókè níbí.” Wọ́n sì gòkè lọ sí ọ̀run nínú àwọsánmà,* àwọn ọ̀tá wọn sì rí wọn.* 13 Ní wákàtí yẹn, ìmìtìtì ilẹ̀ tó lágbára ṣẹlẹ̀, ìdá mẹ́wàá ìlú náà sì ṣubú; ẹgbẹ̀rún méje (7,000) èèyàn ni ìmìtìtì ilẹ̀ náà pa, ẹ̀rù sì ba àwọn yòókù, wọ́n yin Ọlọ́run ọ̀run lógo.

14 Ìyọnu kejì+ ti kọjá. Wò ó! Ìyọnu kẹta ń bọ̀ kíákíá.

15 Áńgẹ́lì keje fun kàkàkí rẹ̀.+ Àwọn ohùn kan ké jáde ní ọ̀run pé: “Ìjọba ayé ti di Ìjọba Olúwa wa+ àti ti Kristi rẹ̀,+ ó sì máa jọba títí láé àti láéláé.”+

16 Àwọn àgbààgbà mẹ́rìnlélógún+ (24) tí wọ́n jókòó sórí ìtẹ́ wọn níwájú Ọlọ́run dojú bolẹ̀, wọ́n sì jọ́sìn Ọlọ́run, 17 wọ́n ní: “A dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ, Jèhófà* Ọlọ́run, Olódùmarè, ẹni tó ti wà tipẹ́, tó sì wà báyìí,+ torí o ti gba agbára ńlá rẹ, o sì ti ń jọba.+ 18 Àmọ́ inú bí àwọn orílẹ̀-èdè, ìwọ náà sì bínú, àkókò wá tó láti ṣèdájọ́ àwọn òkú àti láti san èrè+ fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ tí wọ́n jẹ́ wòlíì+ àti àwọn ẹni mímọ́ àti àwọn tó ń bẹ̀rù orúkọ rẹ, ẹni kékeré àti ẹni ńlá àti láti run àwọn tó ń run ayé.”*+

19 A ṣí ibi mímọ́ tẹ́ńpìlì Ọlọ́run ní ọ̀run, a sì rí àpótí májẹ̀mú rẹ̀ nínú ibi mímọ́ tẹ́ńpìlì rẹ̀.+ Mànàmáná kọ yẹ̀rì, a sì gbọ́ ohùn, ààrá sán, ìmìtìtì ilẹ̀ wáyé, òjò yìnyín rẹpẹtẹ sì rọ̀.

12 Lẹ́yìn náà, mo rí àmì ńlá kan ní ọ̀run: Wọ́n fi oòrùn ṣe obìnrin kan+ lọ́ṣọ̀ọ́,* òṣùpá wà lábẹ́ ẹsẹ̀ rẹ̀, adé oníràwọ̀ méjìlá (12) sì wà ní orí rẹ̀, 2 ó lóyún. Ìrora àti ìnira sì mú kó máa ké jáde bó ṣe ń rọbí.

3 Mo rí àmì míì ní ọ̀run. Wò ó! Dírágónì ńlá+ aláwọ̀ iná, ó ní orí méje àti ìwo mẹ́wàá, adé dáyádémà* méje sì wà ní àwọn orí rẹ̀; 4 ìrù rẹ̀ wọ́ ìdá mẹ́ta àwọn ìràwọ̀+ ojú ọ̀run, ó sì jù wọ́n sí ayé.+ Dírágónì náà dúró pa síwájú obìnrin+ tó fẹ́ bímọ náà, kó lè pa ọmọ tó bá bí jẹ.

5 Obìnrin náà sì bí ọmọ kan,+ ọkùnrin ni, ẹni tó máa fi ọ̀pá irin+ ṣe olùṣọ́ àgùntàn gbogbo orílẹ̀-èdè. A sì já ọmọ náà gbà lọ* sọ́dọ̀ Ọlọ́run àti síbi ìtẹ́ rẹ̀. 6 Obìnrin náà sá lọ sí aginjù, níbi tí Ọlọ́run pèsè àyè sílẹ̀ sí fún un, ibẹ̀ ni wọ́n ti máa bọ́ ọ fún ọ̀tàlélẹ́gbẹ̀fà (1,260) ọjọ́.+

7 Ogun sì bẹ́ sílẹ̀ ní ọ̀run: Máíkẹ́lì*+ àti àwọn áńgẹ́lì rẹ̀ bá dírágónì náà jà, dírágónì náà àti àwọn áńgẹ́lì rẹ̀ sì jà, 8 àmọ́ wọn ò borí,* kò sì sí àyè kankan fún wọn mọ́ ní ọ̀run. 9 A wá ju dírágónì ńlá+ náà sísàlẹ̀, ejò àtijọ́ náà,+ ẹni tí à ń pè ní Èṣù+ àti Sátánì,+ tó ń ṣi gbogbo ilẹ̀ ayé tí à ń gbé lọ́nà;+ a jù ú sí ayé,+ a sì ju àwọn áńgẹ́lì rẹ̀ sísàlẹ̀ pẹ̀lú rẹ̀. 10 Mo gbọ́ tí ohùn kan ké jáde ní ọ̀run pé:

“Ní báyìí, ìgbàlà+ àti agbára dé àti Ìjọba Ọlọ́run wa+ pẹ̀lú àṣẹ Kristi rẹ̀, torí pé a ti ju ẹni tó ń fẹ̀sùn kan àwọn ará wa sísàlẹ̀, ẹni tó ń fẹ̀sùn kàn wọ́n tọ̀sántòru níwájú Ọlọ́run wa!+ 11 Wọ́n ṣẹ́gun rẹ̀  + nítorí ẹ̀jẹ̀ Ọ̀dọ́ Àgùntàn+ náà àti nítorí ọ̀rọ̀ ìjẹ́rìí wọn,+ wọn ò sì nífẹ̀ẹ́ ọkàn* wọn,+ kódà lójú ikú. 12 Torí èyí, ẹ máa yọ̀, ẹ̀yin ọ̀run àti ẹ̀yin tó ń gbé inú wọn! Ayé àti òkun gbé,+ torí pé Èṣù ti sọ̀ kalẹ̀ wá bá yín, ó ń bínú gidigidi, ó mọ̀ pé ìgbà díẹ̀ ló kù fún òun.”+

13 Nígbà tí dírágónì náà rí i pé a ti ju òun sí ayé,+ ó ṣe inúnibíni sí obìnrin+ tó bí ọmọkùnrin náà. 14 Àmọ́ a fún obìnrin náà ní ìyẹ́ méjèèjì ẹyẹ idì ńlá,+ kó lè fò lọ sí àyè rẹ̀ nínú aginjù, níbi tí wọ́n á ti máa bọ́ ọ fún àkókò kan àti àwọn àkókò àti ààbọ̀ àkókò*+ níbi tí ojú ejò náà+ ò tó.

15 Ejò náà sì pọ omi bí odò jáde látẹnu rẹ̀ tẹ̀ lé obìnrin náà, kí odò náà lè gbé e lọ. 16 Àmọ́ ilẹ̀ ran obìnrin náà lọ́wọ́, ilẹ̀ la ẹnu rẹ̀, ó sì gbé odò tí dírágónì náà pọ̀ látẹnu rẹ̀ mì. 17 Dírágónì náà wá bínú gidigidi sí obìnrin náà, ó sì lọ bá àwọn tó ṣẹ́ kù lára ọmọ* rẹ̀ jagun,+ àwọn tó ń pa àṣẹ Ọlọ́run mọ́, tí iṣẹ́ wọn sì jẹ́ láti jẹ́rìí Jésù.+

13 Ó* sì dúró jẹ́ẹ́ lórí iyanrìn òkun.

Mo wá rí ẹranko kan+ tó ń jáde látinú òkun,+ ó ní ìwo mẹ́wàá àti orí méje, adé dáyádémà* mẹ́wàá sì wà lórí àwọn ìwo rẹ̀, àmọ́ àwọn orúkọ tó jẹ́ ọ̀rọ̀ òdì wà ní àwọn orí rẹ̀. 2 Ẹranko tí mo rí sì dà bí àmọ̀tẹ́kùn, àmọ́ ẹsẹ̀ rẹ̀ dà bíi ti bíárì, ẹnu rẹ̀ sì jọ ti kìnnìún. Dírágónì náà+ fún ẹranko náà ní agbára rẹ̀ àti ìtẹ́ rẹ̀, ó sì fún un ní àṣẹ tó pọ̀.+

3 Mo sì rí i, ó dà bíi pé ọgbẹ́ tó lè pa á wà ní ọ̀kan lára àwọn orí rẹ̀, àmọ́ ọgbẹ́ tó lè pa á náà ti jinná,+ gbogbo ayé tẹ̀ lé ẹranko náà, wọ́n sì ń kan sáárá sí i. 4 Wọ́n sì jọ́sìn dírágónì náà torí pé ó fún ẹranko náà ní àṣẹ, wọ́n sì fi àwọn ọ̀rọ̀ yìí jọ́sìn ẹranko yẹn pé: “Ta ló dà bí ẹranko náà, ta ló sì lè bá a jà?” 5 Ó fún un ní ẹnu tó ń sọ àwọn nǹkan ńláńlá àti ọ̀rọ̀ òdì, ó sì fún un ní àṣẹ tó máa lò fún oṣù méjìlélógójì (42).+ 6 Ó la ẹnu rẹ̀, ó fi ń sọ̀rọ̀ òdì+ sí Ọlọ́run, kó lè sọ̀rọ̀ òdì nípa orúkọ rẹ̀ àti ibùgbé rẹ̀, títí kan àwọn tó ń gbé ní ọ̀run.+ 7 A gbà á láyè láti bá àwọn ẹni mímọ́ jagun kó sì ṣẹ́gun wọn,+ a sì fún un ní àṣẹ lórí gbogbo ẹ̀yà, èèyàn, ahọ́n* àti orílẹ̀-èdè. 8 Gbogbo àwọn tó ń gbé ní ayé máa jọ́sìn rẹ̀. Látìgbà ìpìlẹ̀ ayé, a ò kọ orúkọ ẹnì kankan nínú wọn sínú àkájọ ìwé ìyè+ Ọ̀dọ́ Àgùntàn tí wọ́n pa.+

9 Ẹnikẹ́ni tó bá ní etí, kí ó gbọ́.+ 10 Tí ẹnikẹ́ni bá yẹ fún oko ẹrú, ó máa lọ sí oko ẹrú. Tí ẹnikẹ́ni bá máa fi idà pani,* a gbọ́dọ̀ fi idà pa á.+ Ibi tó ti gba pé káwọn ẹni mímọ́+ ní ìfaradà+ àti ìgbàgbọ́+ nìyí.

11 Lẹ́yìn náà, mo rí ẹranko míì tó ń jáde látinú ayé, ó ní ìwo méjì bí ọ̀dọ́ àgùntàn, àmọ́ ó bẹ̀rẹ̀ sí í sọ̀rọ̀ bíi dírágónì.+ 12 Ó ń lo gbogbo àṣẹ tí ẹranko àkọ́kọ́+ ní lójú rẹ̀. Ó sì ń mú kí ayé àti àwọn tó ń gbé inú rẹ̀ jọ́sìn ẹranko àkọ́kọ́ náà, tí ọgbẹ́ rẹ̀ tó lè pani ti jinná.+ 13 Ó ń ṣe àwọn iṣẹ́ àmì tó lágbára, kódà ó ń mú kí iná wá láti ọ̀run sí ayé lójú aráyé.

14 Ó ń ṣi àwọn tó ń gbé ayé lọ́nà, torí àwọn iṣẹ́ àmì tí a gbà á láyè láti ṣe lójú ẹranko náà, bó ṣe ń sọ fún àwọn tó ń gbé ayé pé kí wọ́n ṣe ère+ ẹranko tó ní ọgbẹ́ idà, síbẹ̀ tó sọjí.+ 15 A gbà á láyè pé kó fún ère ẹranko náà ní èémí,* kí ère ẹranko náà lè sọ̀rọ̀, kó sì mú kí wọ́n pa gbogbo àwọn tó kọ̀ láti jọ́sìn ère ẹranko náà.

16 Ó sọ ọ́ di ọ̀ranyàn fún gbogbo èèyàn—ẹni kékeré àti ẹni ńlá, ọlọ́rọ̀ àti òtòṣì, ẹni tó wà lómìnira àti ẹrú—pé kí wọ́n sàmì sí ọwọ́ ọ̀tún wọn tàbí iwájú orí wọn,+ 17 àti pé kí ẹnì kankan má lè rà tàbí tà àfi ẹni tó bá ní àmì náà, orúkọ+ ẹranko náà tàbí nọ́ńbà orúkọ rẹ̀.+ 18 Ibi tó ti gba ọgbọ́n nìyí: Kí ẹni tó ní òye ṣírò nọ́ńbà ẹranko náà, torí pé nọ́ńbà èèyàn ni,* nọ́ńbà rẹ̀ sì ni ọgọ́rùn-ún mẹ́fà àti ọgọ́ta ó lé mẹ́fà (666).+

14 Lẹ́yìn náà, wò ó! mo rí Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà+ tó dúró lórí Òkè Síónì,+ àwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì+ (144,000) wà pẹ̀lú rẹ̀, a kọ orúkọ rẹ̀ àti orúkọ Baba+ rẹ̀ sí iwájú orí wọn. 2 Mo gbọ́ ìró kan tó dún láti ọ̀run bí ìró omi púpọ̀ àti bí ìró ààrá tó rinlẹ̀ gan-an; ìró tí mo gbọ́ náà sì dà bíi ti àwọn akọrin tí wọ́n ń ta háàpù sí orin tí wọ́n ń kọ. 3 Wọ́n sì ń kọ orin kan tó dà bí orin tuntun+ níwájú ìtẹ́ àti níwájú àwọn ẹ̀dá alààyè mẹ́rin+ àti àwọn àgbààgbà náà,+ kò sì sí ẹnì kankan tó lè mọ orin náà àfi àwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì+ (144,000) tí a ti rà látinú ayé. 4 Àwọn yìí kò fi obìnrin sọ ara wọn di aláìmọ́; kódà, wúńdíá ni wọ́n.+ Àwọn ló ń tẹ̀ lé Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà lọ síbikíbi tó bá ń lọ.+ A rà wọ́n+ látinú aráyé, wọ́n sì jẹ́ àkọ́so+ fún Ọlọ́run àti fún Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà, 5 kò sí ẹ̀tàn kankan lẹ́nu wọn; wọn ò sì ní àbààwọ́n.+

6 Mo rí áńgẹ́lì míì tó ń fò lójú ọ̀run,* ó ní ìhìn rere àìnípẹ̀kun láti kéde fún àwọn tó ń gbé ayé, fún gbogbo orílẹ̀-èdè àti ẹ̀yà àti ahọ́n* àti èèyàn.+ 7 Ó ń sọ̀rọ̀ tó dún ketekete pé: “Ẹ bẹ̀rù Ọlọ́run, kí ẹ sì fi ògo fún un, torí wákàtí tó máa ṣèdájọ́ ti dé,+ torí náà, ẹ jọ́sìn Ẹni tó dá ọ̀run àti ayé àti òkun+ àti àwọn ìsun* omi.”

8 Áńgẹ́lì kejì tẹ̀ lé e, ó ń sọ pé: “Ó ti ṣubú! Bábílónì Ńlá+ ti ṣubú,+ ẹni tó mú kí gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè mu nínú wáìnì ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́* ti ìṣekúṣe* rẹ̀!”+

9 Áńgẹ́lì kẹta tẹ̀ lé wọn, ó sì ń fi ohùn tó dún ketekete sọ pé: “Tí ẹnikẹ́ni bá jọ́sìn ẹranko náà+ àti ère rẹ̀, tó sì gba àmì kan sí iwájú orí rẹ̀ tàbí sí ọwọ́ rẹ̀,+ 10 òun náà máa mu nínú wáìnì ìbínú Ọlọ́run tó tú jáde láìní àbùlà sínú ife ìbínú Rẹ̀,+ a sì máa fi iná àti imí ọjọ́+ dá a lóró níwájú àwọn áńgẹ́lì mímọ́ àti níwájú Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà. 11 Àwọn tó ń jọ́sìn ẹranko náà àti ère rẹ̀ àti ẹnikẹ́ni tó bá gba àmì orúkọ rẹ̀,+ èéfín oró* wọn á máa gòkè lọ títí láé àti láéláé,+ wọn ò sì ní sinmi tọ̀sántòru. 12 Ibi tó ti gba pé káwọn ẹni mímọ́ ní ìfaradà nìyí,+ àwọn tó ń pa àwọn àṣẹ Ọlọ́run mọ́ tí wọ́n sì rọ̀ mọ́ ìgbàgbọ́+ Jésù.”

13 Mo gbọ́ tí ohùn kan dún láti ọ̀run pé, “Kọ̀wé pé: Aláyọ̀ ni àwọn òkú tó kú ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú Olúwa+ láti ìsinsìnyí lọ. Àní, ohun tí ẹ̀mí sọ nìyẹn, kí wọ́n sinmi kúrò nínú wàhálà wọn, torí àwọn ohun tí wọ́n ṣe ń bá wọn lọ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀.”*

14 Lẹ́yìn náà, wò ó! mo rí ìkùukùu* funfun kan, ẹnì kan tó rí bí ọmọ èèyàn jókòó sórí ìkùukùu* náà,+ ó dé adé wúrà, dòjé tí ẹnu rẹ̀ mú sì wà ní ọwọ́ rẹ̀.

15 Áńgẹ́lì míì jáde látinú ibi mímọ́ tẹ́ńpìlì, ohùn rẹ̀ dún ketekete bó ṣe ń sọ fún ẹni tó jókòó sórí ìkùukùu pé: “Ti dòjé rẹ bọ̀ ọ́, kí o sì kórè, torí wákàtí ìkórè ti tó, ayé ti gbó dáadáa, ó sì ti tó kórè.”+ 16 Ẹni tó jókòó sórí ìkùukùu ti dòjé rẹ̀ bọ ayé, ó sì kórè ayé.

17 Síbẹ̀, áńgẹ́lì míì jáde látinú ibi mímọ́ tẹ́ńpìlì tó wà ní ọ̀run, dòjé tó mú wà lọ́wọ́ òun náà.

18 Áńgẹ́lì míì tún jáde láti ibi pẹpẹ, ó ní àṣẹ lórí iná. Ó sì fi ohùn tó dún ketekete sọ fún ẹni tí dòjé tó mú wà lọ́wọ́ rẹ̀, pé: “Ti dòjé rẹ tó mú bọ̀ ọ́, kí o sì kó àwọn òṣùṣù èso àjàrà ayé jọ, torí èso àjàrà rẹ̀ ti pọ́n.”+ 19 Áńgẹ́lì náà ti dòjé rẹ̀ bọ ayé, ó kó àjàrà ayé jọ, ó sì jù ú síbi tí ó tóbi tí a ti ń fún wáìnì ti ìbínú Ọlọ́run.+ 20 A sì tẹ àjàrà náà ní òde ìlú náà, ẹ̀jẹ̀ sì tú jáde láti ibi tí a ti ń fún wáìnì náà, ó ga dé ìjánu àwọn ẹṣin, ó sì lọ jìnnà dé ẹgbẹ̀rún kan àti ọgọ́rùn-ún mẹ́fà (1,600) ìwọ̀n Sítédíọ̀mù.*

15 Mo rí àmì míì ní ọ̀run, ó kàmàmà, ó sì yani lẹ́nu, áńgẹ́lì méje+ tí wọ́n ní ìyọnu méje. Àwọn yìí ló kẹ́yìn, torí a máa tipasẹ̀ wọn mú ìbínú Ọlọ́run wá sí òpin.+

2 Mo sì rí ohun kan tó rí bí òkun tó ń dán bíi gíláàsì+ tó dà pọ̀ mọ́ iná, àwọn tó ṣẹ́gun+ ẹranko náà àti ère rẹ̀+ àti nọ́ńbà orúkọ rẹ̀+ dúró níbi òkun tó ń dán bíi gíláàsì náà, wọ́n sì mú háàpù Ọlọ́run dání. 3 Wọ́n ń kọ orin Mósè+ ẹrú Ọlọ́run àti orin Ọ̀dọ́ Àgùntàn+ náà, pé:

“Jèhófà* Ọlọ́run, Olódùmarè,+ àwọn iṣẹ́ rẹ tóbi, ó sì kàmàmà.+ Òdodo àti òótọ́ ni àwọn ọ̀nà rẹ,+ Ọba ayérayé.+ 4 Ta ni kò ní bẹ̀rù rẹ Jèhófà,* tí kò ní yin orúkọ rẹ lógo, torí pé ìwọ nìkan ni adúróṣinṣin?+ Torí gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè máa wá jọ́sìn níwájú rẹ,+ torí a ti fi àwọn àṣẹ òdodo rẹ hàn kedere.”

5 Lẹ́yìn èyí, mo rí i, wọ́n ṣí ibi mímọ́ àgọ́ ẹ̀rí+ ní ọ̀run,+ 6 àwọn áńgẹ́lì méje tí wọ́n ní ìyọnu méje + náà sì jáde látinú ibi mímọ́ náà, wọ́n wọ aṣọ ọ̀gbọ̀* tó mọ́, tó ń tàn yòò, wọ́n sì de ọ̀já wúrà mọ́ àyà wọn. 7 Ọ̀kan lára àwọn ẹ̀dá alààyè mẹ́rin náà fún àwọn áńgẹ́lì méje náà ní abọ́ méje tí wọ́n fi wúrà ṣe tí ìbínú Ọlọ́run,+ ẹni tó wà láàyè títí láé àti láéláé kún inú rẹ̀. 8 Èéfín sì kún ibi mímọ́ torí ògo Ọlọ́run+ àti agbára rẹ̀, ẹnì kankan ò sì lè wọnú ibi mímọ́ náà títí tí ìyọnu méje+ àwọn áńgẹ́lì méje náà fi parí.

16 Mo gbọ́ tí ohùn kan dún ketekete látinú ibi mímọ́ náà,+ ó sọ fún àwọn áńgẹ́lì méje náà pé: “Ẹ lọ da abọ́ méje tí ìbínú Ọlọ́run wà nínú rẹ̀ sórí ayé.”+

2 Àkọ́kọ́ lọ, ó sì da ohun tó wà nínú abọ́ rẹ̀ sórí ayé.+ Egbò tó ń dunni wọra tó sì lè pani+ kọ lu àwọn èèyàn tó ní àmì ẹranko náà,+ tí wọ́n sì ń jọ́sìn ère rẹ̀.+

3 Ìkejì da ohun tó wà nínú abọ́ rẹ̀ sínú òkun.+ Ó sì di ẹ̀jẹ̀+ bí ẹ̀jẹ̀ ẹni tó ti kú, gbogbo ohun alààyè* kú, àní àwọn ohun tó wà nínú òkun.+

4 Ìkẹta da ohun tó wà nínú abọ́ rẹ̀ sínú àwọn odò àti àwọn ìsun* omi.+ Wọ́n sì di ẹ̀jẹ̀.+ 5 Mo gbọ́ tí áńgẹ́lì tó wà lórí àwọn omi sọ pé: “Ìwọ, Ẹni tó ti wà tipẹ́, tó sì wà báyìí,+ Ẹni ìdúróṣinṣin,+ jẹ́ olódodo, torí o ti ṣe àwọn ìdájọ́ yìí,+ 6 torí wọ́n ta ẹ̀jẹ̀ àwọn ẹni mímọ́ àti àwọn wòlíì sílẹ̀,+ o sì ti fún wọn ní ẹ̀jẹ̀ mu;+ ó tọ́ sí wọn.”+ 7 Mo sì gbọ́ tí pẹpẹ náà sọ pé: “Jèhófà* Ọlọ́run, Olódùmarè,+ àní òótọ́ àti òdodo ni àwọn ìdájọ́* rẹ.”+

8 Ìkẹrin da ohun tó wà nínú abọ́ rẹ̀ sórí oòrùn,+ a sì gbà kí oòrùn fi iná jó àwọn èèyàn gbẹ. 9 Ooru tó gbóná janjan náà sì jó àwọn èèyàn náà gbẹ, àmọ́ wọ́n sọ̀rọ̀ òdì sí orúkọ Ọlọ́run, ẹni tó ní àṣẹ lórí àwọn ìyọnu yìí, wọn ò ronú pìwà dà, wọn ò sì yìn ín lógo.

10 Ìkarùn-ún da ohun tó wà nínú abọ́ rẹ̀ sórí ìtẹ́ ẹranko náà. Ni ìjọba rẹ̀ bá ṣókùnkùn,+ wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í gé ahọ́n wọn jẹ torí ìrora wọn, 11 àmọ́ wọ́n sọ̀rọ̀ òdì sí Ọlọ́run ọ̀run nítorí ìrora wọn àti egbò wọn, wọn ò sì ronú pìwà dà nínú àwọn iṣẹ́ wọn.

12 Ìkẹfà da ohun tó wà nínú abọ́ rẹ̀ sínú odò ńlá Yúfírétì,+ omi rẹ̀ sì gbẹ+ láti palẹ̀ ọ̀nà mọ́ fún àwọn ọba+ láti ibi tí oòrùn ti ń yọ.*

13 Mo sì rí i tí àwọn ọ̀rọ̀ àìmọ́ mẹ́ta tó ní ìmísí,* èyí tó rí bí àkèré jáde láti ẹnu dírágónì+ náà àti láti ẹnu ẹranko náà àti láti ẹnu wòlíì èké náà. 14 Ní tòótọ́, wọ́n jẹ́ àwọn ọ̀rọ̀ tí àwọn ẹ̀mí èṣù mí sí, wọ́n ń ṣe àwọn iṣẹ́ àmì,+ wọ́n sì lọ sọ́dọ̀ àwọn ọba gbogbo ilẹ̀ ayé tí à ń gbé, láti kó wọn jọ sí ogun+ ọjọ́ ńlá Ọlọ́run Olódùmarè.+

15 “Wò ó! Mò ń bọ̀ bí olè.+ Aláyọ̀ ni ẹni tó wà lójúfò,+ tó sì wọ aṣọ àwọ̀lékè rẹ̀,* kó má bàa rìn ní ìhòòhò, kí àwọn èèyàn sì wo ìtìjú rẹ̀.”+

16 Wọ́n sì kó wọn jọ sí ibi tí wọ́n ń pè ní Amágẹ́dọ́nì*+ lédè Hébérù.

17 Ìkeje sì da ohun tó wà nínú abọ́ rẹ̀ sínú afẹ́fẹ́. Lẹ́yìn náà, ohùn kan dún ketekete látinú ibi mímọ́+ níbi ìtẹ́ náà, ó sọ pé: “Ó ti rí bẹ́ẹ̀!” 18 Mànàmáná kọ yẹ̀rì, a gbọ́ ohùn, ààrá sán, ìmìtìtì ilẹ̀ tó lágbára sì ṣẹlẹ̀, irú rẹ̀ kò tíì ṣẹlẹ̀ látìgbà téèyàn ti wà ní ayé,+ ìmìtìtì náà lágbára gan-an ó sì lọ jìnnà. 19 Ìlú ńlá náà+ pín sí mẹ́ta, àwọn ìlú àwọn orílẹ̀-èdè sì ṣubú; a sì rántí Bábílónì Ńlá+ níwájú Ọlọ́run, ká lè fún un ní ife wáìnì tí ìbínú Ọlọ́run ń ru nínú rẹ̀.+ 20 Bákan náà, gbogbo erékùṣù sá lọ, a ò sì rí àwọn òkè.+ 21 Lẹ́yìn náà àwọn òkúta yìnyín ńlá já bọ́ lu àwọn èèyàn láti ọ̀run,+ òkúta kọ̀ọ̀kan fẹ́rẹ̀ẹ́ wúwo tó tálẹ́ńtì* kan, àwọn èèyàn náà sì sọ̀rọ̀ òdì sí Ọlọ́run torí ìyọnu yìnyín náà+ àti pé ìyọnu náà pọ̀ lọ́nà tó kàmàmà.

17 Ọ̀kan lára àwọn áńgẹ́lì méje tó ní abọ́ méje+ náà wá, ó sì sọ fún mi pé: “Wá, màá fi ìdájọ́ aṣẹ́wó ńlá tó jókòó lórí omi púpọ̀ hàn ọ́,+ 2 ẹni tí àwọn ọba ayé bá ṣe ìṣekúṣe,*+ tí a sì mú kí àwọn tó ń gbé ayé mu wáìnì ìṣekúṣe* rẹ̀ ní àmupara.”+

3 Ó fi agbára ẹ̀mí gbé mi lọ sínú aginjù kan. Mo sì rí obìnrin kan tó jókòó lórí ẹranko aláwọ̀ rírẹ̀dòdò tó kún fún àwọn orúkọ tó jẹ́ ọ̀rọ̀ òdì, ó ní orí méje àti ìwo mẹ́wàá. 4 Obìnrin náà wọ aṣọ aláwọ̀ rírẹ̀dòdò àti aláwọ̀ pọ́pù,+ a sì fi wúrà, àwọn òkúta iyebíye àti péálì ṣe é lọ́ṣọ̀ọ́,+ ó mú ife tí wọ́n fi wúrà ṣe dání, àwọn ohun ìríra àti àwọn ohun àìmọ́ ìṣekúṣe* rẹ̀ ló kún inú ife náà. 5 Wọ́n kọ orúkọ kan sí iwájú orí rẹ̀, ó jẹ́ àdììtú: “Bábílónì Ńlá, ìyá àwọn aṣẹ́wó+ àti àwọn ohun ìríra ayé.”+ 6 Mo rí i pé obìnrin náà ti mu ẹ̀jẹ̀ àwọn ẹni mímọ́ àti ẹ̀jẹ̀ àwọn ẹlẹ́rìí Jésù ní àmupara.+

Tóò, nígbà tí mo rí i, ó yà mí lẹ́nu gan-an. 7 Áńgẹ́lì náà wá sọ fún mi pé: “Kí nìdí tó fi yà ọ́ lẹ́nu? Màá sọ ohun tó jẹ́ àdììtú nípa obìnrin náà+ fún ọ àti nípa ẹranko tó ń gbé e, èyí tó ní orí méje àti ìwo mẹ́wàá:+ 8 Ẹranko tí ìwọ rí ti wà tẹ́lẹ̀, àmọ́ kò sí, síbẹ̀ ó máa tó jáde látinú ọ̀gbun àìnísàlẹ̀,+ ó sì máa lọ sí ìparun. Nígbà tí àwọn tó ń gbé ayé, ìyẹn àwọn tí a kò kọ orúkọ wọn sínú àkájọ ìwé ìyè+ látìgbà ìpìlẹ̀ ayé, bá sì rí bí ẹranko náà ṣe wà tẹ́lẹ̀, àmọ́ tí kò sí, síbẹ̀ tó tún máa wà, ó máa yà wọ́n lẹ́nu.

9 “Èyí gba pé kí èèyàn ní ọgbọ́n, kó sì lo làákàyè:* Orí méje+ náà túmọ̀ sí òkè méje, níbi tí obìnrin náà jókòó lé. 10 Ọba méje ló wà: Márùn-ún ti ṣubú, ọ̀kan wà, ọ̀kan yòókù kò tíì dé; àmọ́ nígbà tó bá dé, ó gbọ́dọ̀ wà fúngbà díẹ̀. 11 Ẹranko tó wà tẹ́lẹ̀ àmọ́ tí kò sí,+ òun náà ni ọba kẹjọ, àmọ́ ó wá látinú àwọn méje náà, ó sì lọ sí ìparun.

12 “Ìwo mẹ́wàá tí o rí túmọ̀ sí ọba mẹ́wàá, tí kò tíì gba ìjọba, àmọ́ wọ́n gba àṣẹ láti jọba pẹ̀lú ẹranko náà fún wákàtí kan. 13 Èrò kan náà ló wà lọ́kàn wọn, torí náà, wọ́n fún ẹranko náà ní agbára àti àṣẹ wọn. 14 Wọ́n máa bá Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà jà,+ àmọ́, torí òun ni Olúwa àwọn olúwa àti Ọba àwọn ọba,+ Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà máa ṣẹ́gun wọn.+ Bákan náà, àwọn tí a pè tí wọ́n wà pẹ̀lú rẹ̀, tí wọ́n jẹ́ àyànfẹ́ àti olóòótọ́ máa ṣẹ́gun pẹ̀lú.”+

15 Ó sọ fún mi pé: “Àwọn omi tí o rí, níbi tí aṣẹ́wó náà jókòó sí, túmọ̀ sí àwọn èèyàn àti èrò rẹpẹtẹ àti àwọn orílẹ̀-èdè àti àwọn ahọ́n.*+ 16 Ìwo mẹ́wàá+ tí o rí àti ẹranko náà,+ máa kórìíra aṣẹ́wó náà,+ wọ́n máa sọ ọ́ di ahoro, wọ́n á tú u sí ìhòòhò, wọ́n máa jẹ ẹran ara rẹ̀, wọ́n sì máa fi iná sun ún pátápátá.+ 17 Torí Ọlọ́run ti fi sí ọkàn wọn láti ṣe ohun tí òun fẹ́,+ àní láti ṣe ohun kan ṣoṣo tí wọ́n ń rò láti fún ẹranko náà ní ìjọba wọn,+ títí ìgbà tí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run máa ṣẹ délẹ̀délẹ̀. 18 Obìnrin+ tí o rí túmọ̀ sí ìlú ńlá tó ní ìjọba kan tó ń jọba lórí àwọn ọba ayé.”

18 Lẹ́yìn èyí, mo rí áńgẹ́lì míì tó ń sọ̀ kalẹ̀ láti ọ̀run, ó ní àṣẹ tó pọ̀, ògo rẹ̀ sì mú kí ayé mọ́lẹ̀ kedere. 2 Ó sì fi ohùn tó le ké jáde pé: “Ó ti ṣubú! Bábílónì Ńlá ti ṣubú,+ ó sì ti di ibi tí àwọn ẹ̀mí èṣù ń gbé àti ibi tí gbogbo ẹ̀mí àìmọ́* àti gbogbo ẹyẹ àìmọ́ tí a kórìíra ń lúgọ sí!+ 3 Gbogbo orílẹ̀-èdè ti kó sọ́wọ́ rẹ̀ torí wáìnì ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́* ti ìṣekúṣe* rẹ̀,+ àwọn ọba ayé sì bá a ṣe ìṣekúṣe,+ àwọn oníṣòwò* ayé sì di ọlọ́rọ̀ torí ó ń gbé ìgbé ayé gbẹdẹmukẹ lọ́nà tó bùáyà, kò sì nítìjú.”

4 Mo gbọ́ ohùn míì láti ọ̀run, ó sọ pé: “Ẹ jáde kúrò nínú rẹ̀, ẹ̀yin èèyàn mi,+ tí ẹ kò bá fẹ́ pín nínú àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, tí ẹ kò bá sì fẹ́ gbà lára àwọn ìyọnu rẹ̀.+ 5 Torí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ ti ga dé ọ̀run,+ Ọlọ́run sì ti rántí àwọn ìwà àìṣòdodo tó hù.*+ 6 Bó ṣe ṣe sí àwọn míì ni kí ẹ ṣe sí i,+ àní ìlọ́po méjì ohun tó ṣe ni kí ẹ san fún un;+ nínú ife+ tó fi po àdàlù, kí ẹ po ìlọ́po méjì àdàlù náà fún un.+ 7 Bó ṣe ṣe ara rẹ̀ lógo tó àti bó ṣe gbé ìgbé ayé gbẹdẹmukẹ láìnítìjú tó, bẹ́ẹ̀ náà ni kí ẹ jẹ́ kó joró, kó sì ṣọ̀fọ̀ tó. Torí ó ń sọ lọ́kàn rẹ̀ pé: ‘Mo jókòó bí ọbabìnrin, èmi kì í ṣe opó, mi ò sì ní ṣọ̀fọ̀ láé.’+ 8 Ìdí nìyẹn tí àwọn ìyọnu rẹ̀ fi máa dé ní ọjọ́ kan ṣoṣo, ikú àti ọ̀fọ̀ àti ìyàn, a sì máa fi iná sun ún pátápátá,+ torí pé Jèhófà* Ọlọ́run, ẹni tó ṣèdájọ́ rẹ̀, jẹ́ alágbára.+

9 “Àwọn ọba ayé tó bá a ṣe ìṣekúṣe,* tí wọ́n sì jọ gbé ìgbé ayé gbẹdẹmukẹ láìnítìjú máa sunkún, ìbànújẹ́ nítorí rẹ̀ sì máa mú kí wọ́n lu ara wọn, tí wọ́n bá rí èéfín rẹ̀ nígbà tó ń jóná. 10 Wọ́n máa dúró ní òkèèrè torí bó ṣe ń joró bà wọ́n lẹ́rù, wọ́n á sì sọ pé, ‘Ó mà ṣe o, ó mà ṣe o, Bábílónì, ìwọ ìlú ńlá,+ ìwọ ìlú tó lágbára, torí ìdájọ́ rẹ dé ní wákàtí kan!’

11 “Bákan náà, àwọn oníṣòwò ayé ń sunkún, wọ́n sì ń ṣọ̀fọ̀ lórí rẹ̀, torí kò sí ẹni tó máa ra ọjà wọn tó kún fọ́fọ́ mọ́, 12 ọjà tó kún fún wúrà, fàdákà, àwọn òkúta iyebíye, péálì, aṣọ ọ̀gbọ̀ tó dáa,* aṣọ aláwọ̀ pọ́pù, sílíìkì àti aṣọ aláwọ̀ rírẹ̀dòdò; àti gbogbo ohun tí wọ́n fi igi tó ń ta sánsán ṣe; àti oríṣiríṣi àwọn ohun tí wọ́n fi eyín erin ṣe àtàwọn èyí tí wọ́n fi oríṣiríṣi igi iyebíye ṣe àti bàbà, irin pẹ̀lú òkúta mábù; 13 àti igi sínámónì, èròjà tó ń ta sánsán ti Íńdíà, tùràrí, òróró onílọ́fínńdà, oje igi tùràrí, wáìnì, òróró ólífì, ìyẹ̀fun tó kúnná, àlìkámà,* màlúù, àgùntàn, àwọn ẹṣin, kẹ̀kẹ́ ẹrù, àwọn ẹrú àti ẹ̀mí* àwọn èèyàn. 14 Àní èso tó dáa tó wù ọ́* ti kúrò lọ́wọ́ rẹ pẹ̀lú gbogbo nǹkan aládùn, bẹ́ẹ̀ náà làwọn nǹkan tó dáa gan-an ti lọ mọ́ ẹ lọ́wọ́, o ò sì ní rí wọn mọ́ láé.

15 “Àwọn oníṣòwò tó ta àwọn nǹkan yìí, tí wọ́n di ọlọ́rọ̀ láti ara rẹ̀, máa dúró ní òkèèrè torí bó ṣe ń joró bà wọ́n lẹ́rù, wọ́n máa sunkún, wọ́n sì máa ṣọ̀fọ̀, 16 wọ́n á sọ pé, ‘Ó mà ṣe o, ó mà ṣe fún ìlú ńlá náà o, tó wọ aṣọ ọ̀gbọ̀ tó dáa,* tó ní àwọ̀ pọ́pù àti àwọ̀ pupa, tí wọ́n sì fi àwọn ohun ọ̀ṣọ́ oníwúrà ṣe lọ́ṣọ̀ọ́ dáadáa, pẹ̀lú àwọn òkúta iyebíye àti péálì,+ 17 torí pé ọrọ̀ tó pọ̀ tó bẹ́ẹ̀ ti pa run ní wákàtí kan!’

“Gbogbo ọ̀gá àwọn atukọ̀ àti gbogbo àwọn tó máa ń wọkọ̀ òkun àti àwọn òṣìṣẹ́ ọkọ̀ àti gbogbo àwọn tó ń ṣiṣẹ́ lórí òkun, dúró ní òkèèrè, 18 wọ́n ké jáde bí wọ́n ṣe rí èéfín rẹ̀ nígbà tó jóná, wọ́n sọ pé: ‘Ìlú wo ló dà bí ìlú ńlá náà?’ 19 Wọ́n da eruku sórí ara wọn, wọ́n ké jáde, wọ́n ń sunkún, wọ́n sì ń ṣọ̀fọ̀, wọ́n sọ pé: ‘Ó mà ṣe o, ó mà ṣe fún ìlú ńlá náà o, ìlú tí gbogbo àwọn tó ní ọkọ̀ òkun di ọlọ́rọ̀ látinú ọrọ̀ rẹ̀, torí pé ó ti pa run ní wákàtí kan!’+

20 “Máa yọ̀ nítorí rẹ̀, ìwọ ọ̀run+ àti ẹ̀yin ẹni mímọ́,+ ẹ̀yin àpọ́sítélì àti wòlíì, torí pé Ọlọ́run ti kéde ìdájọ́ sórí rẹ̀ nítorí yín!”+

21 Áńgẹ́lì kan tó lágbára wá gbé òkúta kan tó dà bí ọlọ ńlá sókè, ó sì jù ú sínú òkun, ó ní: “Báyìí la ṣe máa yára ju Bábílónì ìlú ńlá náà sísàlẹ̀, a ò sì ní rí i mọ́ láé.+ 22 A ò sì ní gbọ́ ìró àwọn akọrin tí wọ́n ń ta háàpù sí orin tí wọ́n ń kọ nínú rẹ mọ́ àti ìró àwọn olórin, àwọn tó ń fun fèrè àti àwọn tó ń fun kàkàkí. A ò sì ní rí oníṣẹ́ ọnà kankan tó ń ṣe iṣẹ́ èyíkéyìí nínú rẹ mọ́ láé, bẹ́ẹ̀ la ò ní gbọ́ ìró ọlọ kankan nínú rẹ mọ́ láé. 23 Iná fìtílà kankan ò ní tàn nínú rẹ mọ́ láé, a ò sì ní gbọ́ ohùn ọkọ ìyàwó àti ìyàwó nínú rẹ mọ́ láé; torí àwọn ọkùnrin tó wà nípò gíga ní ayé ni àwọn oníṣòwò rẹ, ìwà ìbẹ́mìílò+ rẹ sì ṣi gbogbo orílẹ̀-èdè lọ́nà. 24 Àní inú rẹ̀ ni a ti rí ẹ̀jẹ̀ àwọn wòlíì àti ti àwọn ẹni mímọ́+ àti ti gbogbo àwọn tí wọ́n pa ní ayé.”+

19 Lẹ́yìn èyí, mo gbọ́ ohun kan ní ọ̀run tó dún bí ohùn àwọn tó pọ̀ gan-an. Wọ́n sọ pé: “Ẹ yin Jáà!*+ Ti Ọlọ́run wa ni ìgbàlà àti ògo àti agbára, 2 torí òótọ́ àti òdodo ni àwọn ìdájọ́ rẹ̀.+ Torí ó ti ṣèdájọ́ aṣẹ́wó ńlá tó fi ìṣekúṣe* rẹ̀ ba ayé jẹ́, ó sì ti gbẹ̀san ẹ̀jẹ̀ àwọn ẹrú rẹ̀ tó wà lọ́wọ́ rẹ̀.”*+ 3 Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, wọ́n tún sọ lẹ́ẹ̀kejì pé: “Ẹ yin Jáà!*+ Èéfín rẹ̀ ń lọ sókè títí láé àti láéláé.”+

4 Àwọn àgbààgbà mẹ́rìnlélógún+ (24) àti àwọn ẹ̀dá alààyè mẹ́rin náà  + wólẹ̀, wọ́n sì jọ́sìn Ọlọ́run tó jókòó lórí ìtẹ́, wọ́n sọ pé: “Àmín! Ẹ yin Jáà!”*+

5 Bákan náà, ohùn kan dún láti ibi ìtẹ́ náà, ó sọ pé: “Ẹ máa yin Ọlọ́run wa, gbogbo ẹ̀yin ẹrú rẹ̀,+ tó bẹ̀rù rẹ̀, ẹ̀yin ẹni kékeré àti ẹni ńlá.”+

6 Mo sì gbọ́ ohun tó dún bí ohùn àwọn tó pọ̀ gan-an àti bí ìró omi tó pọ̀ àti bí ìró àwọn ààrá tó rinlẹ̀. Wọ́n sọ pé: “Ẹ yin Jáà,*+ torí Jèhófà* Ọlọ́run wa, Olódùmarè,+ ti bẹ̀rẹ̀ sí í jọba!+ 7 Ẹ jẹ́ ká yọ̀, kí inú wa dùn gan-an, ká sì yìn ín lógo, torí àkókò ìgbéyàwó Ọ̀dọ́ Àgùntàn ti tó, ìyàwó rẹ̀ sì ti múra sílẹ̀. 8 Àní, a ti jẹ́ kó wọ aṣọ ọ̀gbọ̀ tó dáa,* tó ń tàn yòò, tó sì mọ́ tónítóní, aṣọ ọ̀gbọ̀ tó dáa náà dúró fún àwọn iṣẹ́ òdodo àwọn ẹni mímọ́.”+

9 Ó wá sọ fún mi pé, “Kọ̀wé pé: Aláyọ̀ ni àwọn tí a pè wá síbi oúnjẹ alẹ́ ìgbéyàwó Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà.”+ Bákan náà, ó sọ fún mi pé: “Àwọn ọ̀rọ̀ tòótọ́ tí Ọlọ́run sọ nìyí.” 10 Ni mo bá wólẹ̀ níwájú ẹsẹ̀ rẹ̀ láti jọ́sìn rẹ̀. Àmọ́ ó sọ fún mi pé: “Ṣọ́ra! Má ṣe bẹ́ẹ̀!+ Ẹrú bíi tìẹ ni mí àti ti àwọn arákùnrin rẹ tí iṣẹ́ wọn jẹ́ láti jẹ́rìí nípa Jésù.+ Ọlọ́run ni kí o jọ́sìn!+ Torí ìjẹ́rìí nípa Jésù ló ń mí sí àsọtẹ́lẹ̀.”+

11 Mo rí i tí ọ̀run ṣí sílẹ̀, wò ó! ẹṣin funfun kan.+ A pe ẹni tó jókòó sórí rẹ̀ ní Ẹni Tó Ṣeé Gbára Lé+ àti Olóòótọ́,+ ó ń ṣèdájọ́, ó sì ń fi òdodo+ jagun lọ. 12 Ojú rẹ̀ jẹ́ ọwọ́ iná tó ń jó fòfò,+ adé dáyádémà* tó pọ̀ sì wà ní orí rẹ̀. Ó ní orúkọ kan tí a kọ, tí ẹnì kankan ò mọ̀ àfi òun fúnra rẹ̀, 13 ó wọ aṣọ àwọ̀lékè tí ẹ̀jẹ̀ wà lára rẹ̀,* orúkọ tí a sì ń pè é ni Ọ̀rọ̀+ Ọlọ́run. 14 Bákan náà, àwọn ọmọ ogun ọ̀run ń tẹ̀ lé e lórí àwọn ẹṣin funfun, wọ́n wọ aṣọ ọ̀gbọ̀ tó dáa,* tó funfun, tó sì mọ́ tónítóní. 15 Idà tó mú, tó sì gùn jáde láti ẹnu rẹ̀,+ kó lè fi pa àwọn orílẹ̀-èdè, ó sì máa fi ọ̀pá irin ṣe olùṣọ́ àgùntàn wọn.+ Bákan náà, ó ń tẹ ìbínú àti ìrunú Ọlọ́run Olódùmarè níbi tí a ti ń fún wáìnì.+ 16 Orúkọ kan wà tí a kọ sára aṣọ àwọ̀lékè rẹ̀, àní sórí itan rẹ̀, ìyẹn Ọba àwọn ọba àti Olúwa àwọn olúwa.+

17 Mo tún rí áńgẹ́lì kan tó dúró sínú oòrùn, ó fi ohùn tó dún ketekete sọ̀rọ̀, ó sọ fún gbogbo ẹyẹ tó ń fò lójú ọ̀run* pé: “Ẹ wá síbí, ẹ kóra jọ síbi oúnjẹ alẹ́ ńlá ti Ọlọ́run,+ 18 kí ẹ lè jẹ ẹran ara àwọn ọba àti ẹran ara àwọn ọ̀gágun àti ẹran ara àwọn ọkùnrin alágbára+ àti ẹran ara àwọn ẹṣin àti ti àwọn tó jókòó sórí wọn+ àti ẹran ara gbogbo èèyàn, ti ẹni tó wà lómìnira àti ti ẹrú, ti àwọn ẹni kékeré àti ẹni ńlá.”

19 Mo sì rí i tí ẹranko náà àti àwọn ọba ayé pẹ̀lú àwọn ọmọ ogun wọn kóra jọ láti bá ẹni tó jókòó sórí ẹṣin àti àwọn ọmọ ogun rẹ̀ jagun.+ 20 A sì mú ẹranko náà pẹ̀lú wòlíì èké+ tó ṣe àwọn iṣẹ́ àmì níwájú rẹ̀, èyí tó fi ṣi àwọn tó gba àmì ẹranko náà+ lọ́nà àti àwọn tó jọ́sìn ère rẹ̀.+ A ju àwọn méjèèjì láàyè sínú adágún iná tó ń jó, tí a fi imí ọjọ́ sí.+ 21 Àmọ́ a fi idà tó gùn, tó jáde láti ẹnu ẹni tó jókòó sórí ẹṣin pa àwọn yòókù.+ Gbogbo àwọn ẹyẹ sì jẹ ẹran ara wọn yó.+

20 Mo rí i tí áńgẹ́lì kan ń sọ̀ kalẹ̀ láti ọ̀run, ó mú kọ́kọ́rọ́ ọ̀gbun àìnísàlẹ̀  + àti ẹ̀wọ̀n ńlá dání. 2 Ó gbá dírágónì náà+ mú, ejò àtijọ́ náà,+ òun ni Èṣù+ àti Sátánì,+ ó sì dè é fún ẹgbẹ̀rún (1,000) ọdún. 3 Ó jù ú sínú ọ̀gbun àìnísàlẹ̀ náà,+ ó tì í, ó sì gbé èdìdì lé ibi àbáwọlé rẹ̀, kó má bàa ṣi àwọn orílẹ̀-èdè lọ́nà mọ́ títí ẹgbẹ̀rún (1,000) ọdún náà fi máa parí. Lẹ́yìn èyí, a gbọ́dọ̀ tú u sílẹ̀ fúngbà díẹ̀.+

4 Mo rí àwọn ìtẹ́, a sì fún àwọn tó jókòó sórí wọn ní agbára láti ṣèdájọ́. Kódà, mo rí ọkàn* àwọn tí wọ́n pa* torí ẹ̀rí tí wọ́n jẹ́ nípa Jésù, tí wọ́n sì sọ̀rọ̀ nípa Ọlọ́run àti àwọn tí kò jọ́sìn ẹranko náà tàbí ère rẹ̀, tí wọn ò sì gba àmì náà síwájú orí wọn àti ọwọ́ wọn.+ Wọ́n pa dà wà láàyè, wọ́n sì jọba pẹ̀lú Kristi+ fún ẹgbẹ̀rún (1,000) ọdún. 5 (Àwọn òkú yòókù+ ò pa dà wà láàyè títí dìgbà tí ẹgbẹ̀rún [1,000] ọdún náà parí.) Èyí ni àjíǹde àkọ́kọ́.+ 6 Aláyọ̀ àti ẹni mímọ́ ni ẹnikẹ́ni tó nípìn-ín nínú àjíǹde àkọ́kọ́;+ ikú kejì+ kò ní àṣẹ lórí wọn,+ àmọ́ wọ́n máa jẹ́ àlùfáà+ Ọlọ́run àti ti Kristi, wọ́n sì máa jọba pẹ̀lú rẹ̀ fún ẹgbẹ̀rún (1,000) ọdún náà.+

7 Gbàrà tí ẹgbẹ̀rún (1,000) ọdún náà bá parí, a máa tú Sátánì sílẹ̀ kúrò nínú ẹ̀wọ̀n rẹ̀, 8 ó sì máa jáde lọ láti ṣi àwọn orílẹ̀-èdè tó wà ní igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ayé lọ́nà, Gọ́ọ̀gù àti Mágọ́gù, láti kó wọn jọ fún ogun náà. Wọ́n pọ̀ níye bí iyanrìn òkun. 9 Wọ́n lọ káàkiri gbogbo ayé, wọ́n sì wà yí ká ibùdó àwọn ẹni mímọ́ àti ìlú tí a fẹ́ràn. Àmọ́ iná wá láti ọ̀run, ó sì jó wọn run.+ 10 A sì ju Èṣù tó ń ṣì wọ́n lọ́nà sínú adágún iná àti imí ọjọ́, níbi tí ẹranko  + náà àti wòlíì èké náà wà;+ wọ́n á sì máa joró* tọ̀sántòru títí láé àti láéláé.

11 Mo rí ìtẹ́ funfun kan tó tóbi àti Ẹni tó jókòó sórí rẹ̀.+ Ayé àti ọ̀run sá kúrò níwájú rẹ̀,+ kò sì sí àyè kankan fún wọn. 12 Mo rí àwọn òkú, ẹni ńlá àti ẹni kékeré, wọ́n dúró síwájú ìtẹ́ náà, a sì ṣí àwọn àkájọ ìwé sílẹ̀. Àmọ́ a ṣí àkájọ ìwé míì; àkájọ ìwé ìyè ni.+ A fi àwọn ohun tí a kọ sínú àkájọ ìwé náà ṣèdájọ́ àwọn òkú bí iṣẹ́ ọwọ́ wọn ṣe rí.+ 13 Òkun yọ̀ǹda àwọn òkú tó wà nínú rẹ̀, ikú àti Isà Òkú* yọ̀ǹda àwọn òkú tó wà nínú wọn, a sì ṣèdájọ́ ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn bí iṣẹ́ ọwọ́ wọn ṣe rí.+ 14 A sì ju ikú àti Isà Òkú* sínú adágún iná.+ Èyí túmọ̀ sí ikú kejì,+ adágún iná náà.+ 15 Bákan náà, a ju ẹnikẹ́ni tí a kò rí i pé wọ́n kọ orúkọ rẹ̀ sínú ìwé ìyè+ sínú adágún iná náà.+

21 Mo rí ọ̀run tuntun àti ayé tuntun;+ torí ọ̀run tó wà tẹ́lẹ̀ àti ayé tó wà tẹ́lẹ̀ ti kọjá lọ,+ kò sì sí òkun mọ́.+ 2 Bákan náà mo rí ìlú mímọ́ náà, Jerúsálẹ́mù Tuntun, ó ń ti ọ̀run sọ̀ kalẹ̀ látọ̀dọ̀ Ọlọ́run,+ bí ìyàwó tí a ṣe lọ́ṣọ̀ọ́ fún ọkọ rẹ̀.+ 3 Ni mo bá gbọ́ ohùn kan tó dún ketekete látorí ìtẹ́ náà, ó sọ pé: “Wò ó! Àgọ́ Ọlọ́run wà pẹ̀lú aráyé, á máa bá wọn gbé, wọ́n á sì jẹ́ èèyàn rẹ̀. Ọlọ́run fúnra rẹ̀ máa wà pẹ̀lú wọn.+ 4 Ó máa nu gbogbo omijé kúrò ní ojú wọn,+ ikú ò ní sí mọ́,+ kò ní sí ọ̀fọ̀ tàbí ẹkún tàbí ìrora mọ́.+ Àwọn nǹkan àtijọ́ ti kọjá lọ.”

5 Ẹni tó jókòó sórí ìtẹ́+ sọ pé: “Wò ó! Mò ń sọ ohun gbogbo di tuntun.”+ Ó tún sọ pé: “Kọ ọ́ sílẹ̀, torí àwọn ọ̀rọ̀ yìí ṣeé gbára lé,* òótọ́ sì ni.” 6 Ó sọ fún mi pé: “Wọ́n ti rí bẹ́ẹ̀! Èmi ni Ááfà àti Ómégà,* ìbẹ̀rẹ̀ àti òpin.+ Màá fún ẹnikẹ́ni tí òùngbẹ ń gbẹ ní omi látinú ìsun* omi ìyè lọ́fẹ̀ẹ́.*+ 7 Ẹnikẹ́ni tó bá ń ṣẹ́gun máa jogún àwọn nǹkan yìí, màá jẹ́ Ọlọ́run rẹ̀, ó sì máa jẹ́ ọmọ mi. 8 Àmọ́ ní ti àwọn ojo àti àwọn tí kò ní ìgbàgbọ́+ àti àwọn tí èérí wọn ń ríni lára àti àwọn apààyàn+ àti àwọn oníṣekúṣe*+ àti àwọn tó ń bá ẹ̀mí lò àti àwọn abọ̀rìṣà àti gbogbo òpùrọ́,+ ìpín wọn máa wà nínú adágún tó ń jó, tí a fi imí ọjọ́ sí.+ Èyí túmọ̀ sí ikú kejì.”+

9 Ọ̀kan nínú àwọn áńgẹ́lì méje tó gbé abọ́ méje dání tí ìyọnu méje tó kẹ́yìn+ kún inú rẹ̀ wá sọ́dọ̀ mi, ó sọ fún mi pé: “Wá, màá sì fi ìyàwó hàn ọ́, aya Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà.”+ 10 Lẹ́yìn náà, ó gbé mi nínú agbára ẹ̀mí lọ sí òkè ńlá kan tó ga fíofío, ó fi Jerúsálẹ́mù ìlú mímọ́ náà hàn mí, tó ń ti ọ̀run sọ̀ kalẹ̀ látọ̀dọ̀ Ọlọ́run,+ 11 ó sì ní ògo Ọlọ́run.+ Ó ń tàn yanran bí òkúta tó ṣeyebíye jù lọ, bí òkúta jásípérì tó ń dán gbinrin bíi kírísítálì.+ 12 Ó ní ògiri ńlá tó ga fíofío, ó sì ní ẹnubodè méjìlá (12), àwọn áńgẹ́lì méjìlá (12) wà ní àwọn ẹnubodè náà, a sì kọ orúkọ àwọn ẹ̀yà méjìlá (12) àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sí àwọn ẹnubodè náà. 13 Ẹnubodè mẹ́ta wà ní ìlà oòrùn, mẹ́ta ní àríwá, mẹ́ta ní gúúsù àti mẹ́ta ní ìwọ̀ oòrùn.+ 14 Ògiri ìlú náà tún ní òkúta ìpìlẹ̀ méjìlá (12), orúkọ méjìlá (12) àwọn àpọ́sítélì méjìlá (12)+ ti Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà sì wà lára wọn.

15 Ẹni tó ń bá mi sọ̀rọ̀ mú ọ̀pá esùsú tí a fi wúrà ṣe dání kó lè fi ṣe ìwọ̀n, láti wọn ìlú náà àti àwọn ẹnubodè rẹ̀ àti ògiri rẹ̀.+ 16 Ìlú náà ní igun mẹ́rin tó dọ́gba, gígùn rẹ̀ àti fífẹ̀ rẹ̀ tóbi lọ́gbọọgba. Ó fi ọ̀pá esùsú náà wọn ìlú náà, ẹgbẹ̀rún méjìlá (12,000) ìwọ̀n Sítédíọ̀mù;* gígùn àti fífẹ̀ àti gíga rẹ̀ jẹ́ ọgbọọgba. 17 Bákan náà, ó wọn ògiri rẹ̀, ó jẹ́ ogóje ó lé mẹ́rin (144) ìgbọ̀nwọ́,* bí èèyàn ṣe ń wọn nǹkan àti bí àwọn áńgẹ́lì ṣe ń wọn nǹkan. 18 Òkúta jásípérì+ ni wọ́n fi ṣe ògiri rẹ̀, ìlú náà sì jẹ́ ògidì wúrà bíi gíláàsì tó mọ́ kedere. 19 A fi oríṣiríṣi òkúta iyebíye ṣe àwọn ìpìlẹ̀ ògiri ìlú náà lọ́ṣọ̀ọ́: ìpìlẹ̀ àkọ́kọ́ jẹ́ jásípérì, ìkejì jẹ́ sàfáyà, ìkẹta jẹ́ kásídónì, ìkẹrin jẹ́ ẹ́mírádì, 20 ìkarùn-ún jẹ́ sádónísì, ìkẹfà jẹ́ sádíọ́sì, ìkeje jẹ́ kírísóláítì, ìkẹjọ jẹ́ bérílì, ìkẹsàn-án jẹ́ tópásì, ìkẹwàá jẹ́ kírísópírásì, ìkọkànlá jẹ́ háyásíǹtì, ìkejìlá jẹ́ ámétísì. 21 Bákan náà, ẹnubodè méjìlá (12) náà jẹ́ péálì méjìlá (12); péálì kan la fi ṣe ẹnubodè kọ̀ọ̀kan. Ọ̀nà tó bọ́ sí gbangba ní ìlú náà jẹ́ ògidì wúrà, bíi gíláàsì tí a lè rí òdìkejì rẹ̀ kedere.

22 Mi ò rí tẹ́ńpìlì kankan nínú rẹ̀, torí Jèhófà* Ọlọ́run Olódùmarè+ ni tẹ́ńpìlì rẹ̀ àti Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà. 23 Ìlú náà ò nílò kí oòrùn tàbí òṣùpá tàn sórí rẹ̀, torí ògo Ọlọ́run mú kó mọ́lẹ̀ rekete,+ Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà sì ni fìtílà rẹ̀.+ 24 Àwọn orílẹ̀-èdè máa rìn nínú ìmọ́lẹ̀ rẹ̀,+ àwọn ọba ayé sì máa mú ògo wọn wá sínú rẹ̀. 25 A ò ní ti ẹnubodè rẹ̀ rárá ní ọ̀sán, torí pé ilẹ̀ ò ní ṣú níbẹ̀.+ 26 Wọ́n sì máa mú ògo àti ọlá àwọn orílẹ̀-èdè wá sínú rẹ̀.+ 27 Àmọ́ ohunkóhun tó ní àbààwọ́n àti ẹnikẹ́ni tó ń hùwà tó ń ríni lára, tó sì ń tanni jẹ kò ní wọnú rẹ̀ rárá;+ àwọn tí a kọ orúkọ wọn sínú àkájọ ìwé ìyè Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà nìkan ló máa wọnú rẹ̀.+

22 Ó wá fi odò omi ìyè+ kan hàn mí, tó mọ́ rekete bíi kírísítálì, tó ń ṣàn jáde láti ibi ìtẹ́ Ọlọ́run àti ti Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà  + 2 wá sí àárín ọ̀nà rẹ̀ tó bọ́ sí gbangba. Àwọn igi ìyè tó ń so èso méjìlá (12) sì wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ méjèèjì odò náà, wọ́n ń so èso lóṣooṣù. Ewé àwọn igi náà sì wà fún mímú àwọn orílẹ̀-èdè lára dá.+

3 Kò ní sí ègún kankan mọ́. Àmọ́ ìtẹ́ Ọlọ́run àti ti Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà+ máa wà ní ìlú náà, àwọn ẹrú rẹ̀ á sì máa ṣe iṣẹ́ ìsìn mímọ́ fún un; 4 wọ́n máa rí ojú rẹ̀,+ orúkọ rẹ̀ sì máa wà níwájú orí wọn.+ 5 Bákan náà, ilẹ̀ ò ní ṣú mọ́,+ wọn ò sì nílò ìmọ́lẹ̀ fìtílà tàbí ìmọ́lẹ̀ oòrùn, torí pé Jèhófà* Ọlọ́run máa tan ìmọ́lẹ̀ sórí wọn,+ wọ́n sì máa jọba títí láé àti láéláé.+

6 Ó sọ fún mi pé: “Àwọn ọ̀rọ̀ yìí ṣeé gbára lé,* òótọ́ sì ni;+ kódà, Jèhófà* Ọlọ́run tó mí sí àwọn wòlíì+ ti rán áńgẹ́lì rẹ̀ láti fi àwọn nǹkan tó gbọ́dọ̀ ṣẹlẹ̀ láìpẹ́ han àwọn ẹrú rẹ̀. 7 Wò ó! mò ń bọ̀ kíákíá.+ Aláyọ̀ ni ẹnikẹ́ni tó bá ń pa àwọn ọ̀rọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ àkájọ ìwé yìí mọ́.”+

8 Èmi Jòhánù fi ojú ara mi rí àwọn nǹkan yìí, mo sì fi etí ara mi gbọ́ ọ. Nígbà tí mo gbọ́, tí mo sì rí i, mo wólẹ̀ láti jọ́sìn ní ẹsẹ̀ áńgẹ́lì tó ń fi àwọn nǹkan yìí hàn mí. 9 Àmọ́ ó sọ fún mi pé: “Ṣọ́ra! Má ṣe bẹ́ẹ̀! Ẹrú bíi tìẹ ni mí àti ti àwọn arákùnrin rẹ wòlíì àti àwọn tó ń pa àwọn ọ̀rọ̀ inú àkájọ ìwé yìí mọ́. Ọlọ́run ni kí o jọ́sìn.”+

10 Ó tún sọ fún mi pé: “Má ṣe gbé èdìdì lé àwọn ọ̀rọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ àkájọ ìwé yìí, torí àkókò tí a yàn ti sún mọ́lé. 11 Kí ẹni tó jẹ́ aláìṣòdodo máa ṣe àìṣòdodo, kí ẹni tó jẹ́ ẹlẹ́gbin má sì jáwọ́ nínú ẹ̀gbin rẹ̀; àmọ́ kí olódodo túbọ̀ máa ṣe òdodo, kí ẹni mímọ́ sì túbọ̀ máa jẹ́ mímọ́.

12 “‘Wò ó! Mò ń bọ̀ kíákíá, èrè tí mo sì ń fúnni wà pẹ̀lú mi, láti san ẹ̀san fún kálukú bí iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀ bá ṣe rí.+ 13 Èmi ni Ááfà àti Ómégà,*+ ẹni àkọ́kọ́ àti ẹni ìkẹyìn, ìbẹ̀rẹ̀ àti òpin. 14 Aláyọ̀ ni àwọn tó fọ aṣọ wọn,+ kí wọ́n lè ní àṣẹ láti lọ síbi àwọn igi ìyè,+ kí wọ́n sì lè gba ẹnubodè wọnú ìlú náà.+ 15 Ìta ni àwọn ajá* wà àti àwọn tó ń bá ẹ̀mí lò àti àwọn oníṣekúṣe* àti àwọn apààyàn àti àwọn abọ̀rìṣà àti gbogbo àwọn tó fẹ́ràn irọ́, tí wọ́n sì ń parọ́.’+

16 “‘Èmi Jésù rán áńgẹ́lì mi láti jẹ́rìí àwọn nǹkan yìí fún ọ nítorí àwọn ìjọ. Èmi ni gbòǹgbò àti ọmọ Dáfídì+ àti ìràwọ̀ òwúrọ̀ tó mọ́lẹ̀ rekete.’”+

17 Ẹ̀mí àti ìyàwó+ ń sọ pé, “Máa bọ̀!” kí ẹnikẹ́ni tó ń gbọ́ sọ pé, “Máa bọ̀!” kí ẹnikẹ́ni tí òùngbẹ ń gbẹ sì máa bọ̀;+ kí ẹnikẹ́ni tó bá fẹ́, gba omi ìyè lọ́fẹ̀ẹ́.+

18 “Mò ń jẹ́rìí fún gbogbo ẹni tó ń gbọ́ àwọn ọ̀rọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ àkájọ ìwé yìí pé: Tí ẹnikẹ́ni bá fi kún àwọn nǹkan yìí,+ Ọlọ́run máa fi àwọn ìyọnu tó wà nínú àkájọ ìwé yìí kún un fún ẹni náà;+ 19 tí ẹnikẹ́ni bá sì yọ ohunkóhun kúrò nínú àwọn ọ̀rọ̀ àkájọ ìwé àsọtẹ́lẹ̀ yìí, Ọlọ́run máa yọ ìpín rẹ̀ kúrò nínú àwọn igi ìyè+ àti kúrò nínú ìlú mímọ́ náà,+ àwọn nǹkan tí a kọ nípa wọn sínú àkájọ ìwé yìí.

20 “Ẹni tó jẹ́rìí nípa àwọn nǹkan yìí sọ pé, ‘Àní, mò ń bọ̀ kíákíá.’”+

“Àmín! Máa bọ̀, Jésù Olúwa.”

21 Kí inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Jésù Olúwa wà pẹ̀lú àwọn ẹni mímọ́.

Tàbí “Ìṣípayá; Ohun tí a ṣí.”

Tàbí “àwọsánmà.”

Wo Àfikún A5.

Tàbí “ìbẹ̀rẹ̀ àti òpin.” Ááfà ni lẹ́tà àkọ́kọ́ nínú álífábẹ́ẹ̀tì èdè Gíríìkì, Ómégà sì ni lẹ́tà tó gbẹ̀yìn.

Tàbí “Hédíìsì,” ìyẹn ibojì aráyé. Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.

Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.

Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.

Lédè Gíríìkì, por·neiʹa. Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.

Tàbí “bí ìmọ̀lára ẹni ṣe rí nínú lọ́hùn-ún.” Ní Grk., “àwọn kíndìnrín.”

Tàbí “wọ́n kàn mọ̀ ẹ́ sí ẹni tó wà láàyè.”

Tàbí “ṣe àwọn iṣẹ́ rẹ láṣepé.”

Tàbí “máa rántí bí o ṣe gbà àti bí o ṣe gbọ́.”

Ní Grk., “àwọn orúkọ díẹ̀ kan.”

Tàbí “pa orúkọ rẹ̀ rẹ́.”

Tàbí “forí balẹ̀.”

Tàbí kó jẹ́, “o tẹ̀ lé àpẹẹrẹ ìfaradà mi.”

Tàbí “òkúta aláwọ̀ pupa tó ṣeyebíye.”

Tàbí “ní àárín pẹ̀lú ìtẹ́ náà.”

Wo Àfikún A5.

Wo Àfikún A5.

Ní Grk., “nínú àti lóde.”

Tàbí “èdè.”

Tàbí “ọ̀kẹ́ àìmọye lọ́nà ọ̀kẹ́ àìmọye.”

Ní Grk., “ọrun.”

Wo Àfikún B14.

Tàbí “wíìtì.”

Ẹyọ owó fàdákà ti ilẹ̀ Róòmù tí òṣìṣẹ́ ń gbà fún iṣẹ́ ọjọ́ kan. Wo Àfikún B14.

Tàbí “Hédíìsì,” ìyẹn ibojì aráyé. Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.

Ó ṣe kedere pé ẹ̀jẹ̀ tí wọ́n tú sórí pẹpẹ ló ń tọ́ka sí. Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.

Ní Grk., “aṣọ àpò ìdọ̀họ.”

Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ irun ewúrẹ́.

Tàbí “ìlà oòrùn.”

Tàbí “ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn.”

Tàbí “àwọn èdè.”

Tàbí “àwọn orísun.”

Tàbí “ohun tí wọ́n fi ń sun tùràrí.”

Tàbí “àwọn ẹ̀dá abẹ̀mí.”

Tàbí “àwọn orísun omi.”

Ìyẹn, igi kan tó korò gan-an.

Tàbí “ihò tó já sí.”

Tàbí “Ó ṣí ihò tó já sí.”

Ó túmọ̀ sí “Ìparun.”

Ó túmọ̀ sí “Apanirun.”

Tàbí “ọ̀kẹ́ kan (20,000) lọ́nà ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá (10,000),” ìyẹn, igba mílíọ̀nù (200,000,000).

Lédè Gíríìkì, por·neiʹa. Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.

Tàbí “àwọsánmà.”

Tàbí “fi ìkùukùu bò.”

Ní Grk., “àtẹ́lẹsẹ̀.”

Tàbí “àwọn èdè.”

Ìyẹn, koríko etí omi.

Tàbí “ọ̀pá ìdíwọ̀n.”

Ní Grk., “aṣọ àpò ìdọ̀họ.”

Tàbí “ọ̀run.”

Tàbí “àwọn èdè.”

Tàbí “ìkùukùu.”

Tàbí “sì ń wò wọ́n.”

Wo Àfikún A5.

Tàbí “láti pa àwọn tó ń pa ayé run.”

Tàbí “Obìnrin kan wọ oòrùn bí aṣọ.”

Tàbí “àwọn ìwérí ọba.”

Tàbí “mú ọmọ náà lọ.”

Ó túmọ̀ sí “Ta Ló Dà Bí Ọlọ́run?”

Tàbí kó jẹ́, “àmọ́ wọ́n ṣẹ́gun rẹ̀ [ìyẹn, dírágónì náà].”

Tàbí “ẹ̀mí.” Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.

Ìyẹn, àkókò mẹ́ta àti ààbọ̀.

Ní Grk., “èso.”

Ìyẹn, dírágónì náà.

Tàbí “àwọn ìwérí ọba.”

Tàbí “èdè.”

Tàbí kó jẹ́, “Tí a bá máa fi idà pa ẹnikẹ́ni.”

Tàbí “ẹ̀mí.”

Tàbí “nọ́ńbà aráyé.”

Tàbí “ní agbedeméjì ọ̀run; ní òkè.”

Tàbí “èdè.”

Tàbí “àwọn orísun.”

Tàbí “ìbínú.”

Lédè Gíríìkì, por·neiʹa. Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.

Tàbí “àhámọ́; ẹ̀wọ̀n.”

Tàbí “ń tẹ̀ lé wọn bí wọ́n ṣe ń lọ.”

Tàbí “àwọsánmà.”

Tàbí “àwọsánmà.”

Nǹkan bíi kìlómítà 296 (mítà 184). Sítédíọ̀mù kan jẹ́ mítà 185 (606.95 ẹsẹ̀ bàtà). Wo Àfikún B14.

Wo Àfikún A5.

Wo Àfikún A5.

Tàbí “aṣọ àtàtà.”

Tàbí “ọkàn.”

Tàbí “orísun.”

Wo Àfikún A5.

Tàbí “ìpinnu ìdájọ́.”

Tàbí “láti ìlà oòrùn.”

Ní Grk., “àwọn ẹ̀mí àìmọ́ mẹ́ta.”

Ní Grk., “tó sì pa aṣọ àwọ̀lékè rẹ̀ mọ́.”

Lédè Gíríìkì, Har Ma·ge·donʹ, ó wá látinú ọ̀rọ̀ èdè Hébérù tó túmọ̀ sí “Òkè Mẹ́gídò.”

Tálẹ́ńtì Gíríìkì kan jẹ́ kìlógíráàmù 20.4. Wo Àfikún B14.

Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.

Lédè Gíríìkì, por·neiʹa. Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.

Lédè Gíríìkì, por·neiʹa. Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.

Tàbí “ní àròjinlẹ̀.”

Tàbí “àwọn èdè.”

Tàbí kó jẹ́, “èémí; èémí àmíjáde; ọ̀rọ̀ onímìísí.”

Tàbí “ìbínú.”

Lédè Gíríìkì, por·neiʹa. Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.

Tàbí “àwọn oníṣòwò tó ń rìnrìn àjò.”

Tàbí “àwọn ọ̀ràn tó dá.”

Wo Àfikún A5.

Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.

Tàbí “aṣọ àtàtà.”

Tàbí “wíìtì.”

Tàbí “ọkàn.”

Tàbí “tí ọkàn rẹ fẹ́.”

Tàbí “aṣọ àtàtà.”

Tàbí “Halelúyà!” “Jáà” ni ìkékúrú Jèhófà.

Lédè Gíríìkì, por·neiʹa. Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.

Ní Grk., “láti ọwọ́ rẹ̀.”

Tàbí “Halelúyà!” “Jáà” ni ìkékúrú Jèhófà.

Tàbí “Halelúyà!” “Jáà” ni ìkékúrú Jèhófà.

Tàbí “Halelúyà!” “Jáà” ni ìkékúrú Jèhófà.

Wo Àfikún A5.

Tàbí “aṣọ àtàtà.”

Tàbí “àwọn ìwérí ọba.”

Tàbí kó jẹ́, “tí ẹ̀jẹ̀ ti ta sí.”

Tàbí “aṣọ àtàtà.”

Tàbí “ní agbedeméjì ọ̀run; ní òkè.”

Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀ àti àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé Ifi 6:9.

Ní Grk., “àwọn tí wọ́n fi àáké pa.”

Tàbí “dè wọ́n; fi wọ́n sẹ́wọ̀n.” Wo Ifi 14:11 àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé.

Tàbí “Hédíìsì,” ìyẹn ibojì aráyé. Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.

Tàbí “Hédíìsì,” ìyẹn ibojì aráyé. Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.

Tàbí “ṣeé gbọ́kàn lé.”

Ááfà ni lẹ́tà àkọ́kọ́ nínú álífábẹ́ẹ̀tì èdè Gíríìkì, Ómégà sì ni lẹ́tà tó gbẹ̀yìn.

Tàbí “orísun.”

Tàbí “láìsan ohunkóhun.”

Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀, “Ìṣekúṣe.”

Nǹkan bíi kìlómítà 2,220 (máìlì 1,379). Sítédíọ̀mù kan jẹ́ mítà 185 (606.95 ẹsẹ̀ bàtà). Wo Àfikún B14.

Nǹkan bíi mítà 64 (ẹsẹ̀ bàtà 210). Wo Àfikún B14.

Wo Àfikún A5.

Wo Àfikún A5.

Tàbí “ṣeé gbọ́kàn lé.”

Wo Àfikún A5.

Ááfà ni lẹ́tà àkọ́kọ́ nínú álífábẹ́ẹ̀tì èdè Gíríìkì, Ómégà sì ni lẹ́tà tó gbẹ̀yìn.

Ìyẹn, àwọn tí ohun tí wọ́n ń ṣe burú jáì lójú Ọlọ́run.

Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀, “Ìṣekúṣe.”

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́