ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • nwt Ìṣe 1:1-28:31
  • Ìṣe

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìṣe
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
Ìṣe

ÌṢE ÀWỌN ÀPỌ́SÍTÉLÌ

1 Tìófílọ́sì, nínú ìwé àkọ́kọ́ tí mo kọ sí ọ, mo sọ nípa gbogbo ohun tí Jésù ṣe àti ohun tí ó kọ́ni+ 2 títí di ọjọ́ tí Ọlọ́run gbé e lọ sókè,+ lẹ́yìn tó ti tipasẹ̀ ẹ̀mí mímọ́ sọ ohun tí àwọn àpọ́sítélì tó ti yàn máa ṣe.+ 3 Lẹ́yìn tó ti jìyà, ó fara hàn wọ́n láàyè nípasẹ̀ ọ̀pọ̀ ẹ̀rí tó dájú.+ Wọ́n rí i jálẹ̀ ogójì (40) ọjọ́, ó sì ń sọ̀rọ̀ nípa Ìjọba Ọlọ́run.+ 4 Nígbà tó ń bá wọn ṣèpàdé, ó pàṣẹ fún wọn pé: “Ẹ má ṣe kúrò ní Jerúsálẹ́mù,+ àmọ́ ẹ dúró de ohun tí Baba ti ṣèlérí,+ èyí tí ẹ gbọ́ lẹ́nu mi; 5 lóòótọ́, Jòhánù fi omi batisí, àmọ́ a ó fi ẹ̀mí mímọ́ batisí yín+ láìpẹ́ ọjọ́.”

6 Nígbà tí wọ́n pé jọ, wọ́n bi í pé: “Olúwa, ṣé àkókò yìí lo máa dá ìjọba pa dà fún Ísírẹ́lì?”+ 7 Ó sọ fún wọn pé: “Kì í ṣe tiyín láti mọ ìgbà tàbí àsìkò tí Baba ti fi sí ìkáwọ́* rẹ̀.+ 8 Àmọ́, ẹ ó gba agbára nígbà tí ẹ̀mí mímọ́ bá bà lé yín,+ ẹ ó sì jẹ́ ẹlẹ́rìí+ mi ní Jerúsálẹ́mù,+ ní gbogbo Jùdíà àti Samáríà+ àti títí dé ibi tó jìnnà jù lọ ní ayé.”*+ 9 Lẹ́yìn tó ti sọ àwọn nǹkan yìí, bí wọ́n ṣe ń wò ó, a gbé e sókè, àwọsánmà sì gbà á lọ mọ́ wọn lójú.+ 10 Bí wọ́n ṣe tẹjú mọ́ sánmà nígbà tó ń lọ, lójijì ọkùnrin méjì tó wọ aṣọ funfun+ dúró lẹ́gbẹ̀ẹ́ wọn, 11 wọ́n sì sọ pé: “Ẹ̀yin èèyàn Gálílì, kí ló dé tí ẹ dúró tí ẹ̀ ń wojú sánmà? Jésù yìí tí a gbà sókè kúrò lọ́dọ̀ yín sínú sánmà yóò wá ní irú ọ̀nà kan náà bí ẹ ṣe rí i tó ń lọ sínú sánmà.”

12 Lẹ́yìn náà, wọ́n pa dà sí Jerúsálẹ́mù+ láti òkè tí wọ́n ń pè ní Òkè Ólífì, tó wà nítòsí Jerúsálẹ́mù, ó tó ìrìn ọjọ́ sábáàtì kan. 13 Nígbà tí wọ́n dé, wọ́n lọ sínú yàrá òkè tí wọ́n ń gbé. Àwọn ni: Pétérù pẹ̀lú Jòhánù àti Jémíìsì àti Áńdérù, Fílípì àti Tọ́másì, Bátólómíù àti Mátíù, Jémíìsì ọmọ Áfíọ́sì àti Símónì onítara pẹ̀lú Júdásì ọmọ Jémíìsì.+ 14 Gbogbo wọn tẹra mọ́ àdúrà pẹ̀lú èrò tó ṣọ̀kan, àwọn àti àwọn obìnrin kan+ pẹ̀lú Màríà ìyá Jésù àti àwọn arákùnrin rẹ̀.+

15 Lásìkò yẹn, Pétérù dìde láàárín àwọn ará, (iye àwọn èèyàn* náà lápapọ̀ jẹ́ nǹkan bí ọgọ́fà [120]) ó sì sọ pé: 16 “Ẹ̀yin èèyàn, ẹ̀yin ará, ó pọn dandan kí ìwé mímọ́ ṣẹ, èyí tí ẹ̀mí mímọ́ gba ẹnu Dáfídì sọ nípa Júdásì,+ ẹni tó ṣamọ̀nà àwọn tó wá mú Jésù.+ 17 Nítorí a ti kà á mọ́ wa,+ ó sì ní ìpín nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ yìí. 18 (Ọkùnrin yìí fi owó iṣẹ́ ibi+ rẹ̀ ra ilẹ̀ kan, àmọ́, ó fi orí sọlẹ̀, ikùn rẹ̀ bẹ́,* gbogbo ìfun rẹ̀ sì tú síta.+ 19 Gbogbo àwọn tó ń gbé Jerúsálẹ́mù gbọ́ nípa rẹ̀, wọ́n sì pe ilẹ̀ náà ní Ákélídámà ní èdè wọn, ìyẹn, “Ilẹ̀ Ẹ̀jẹ̀.”) 20 Nítorí ó wà lákọsílẹ̀ nínú ìwé Sáàmù pé, ‘Kí ibi tó ń gbé di ahoro, kí ó má ṣe sí ẹnì kankan tí á máa gbé inú rẹ̀’+ àti pé, ‘Kí ẹlòmíì gba iṣẹ́ àbójútó rẹ̀.’+ 21 Nítorí náà, ó pọn dandan pé nínú àwọn ọkùnrin tó wà pẹ̀lú wa ní gbogbo àkókò tí Jésù Olúwa fi ṣe iṣẹ́ rẹ̀* láàárín wa, 22 látìgbà tí Jòhánù ti ṣèrìbọmi fún un+ títí di ọjọ́ tí a gbé e sókè kúrò lọ́dọ̀ wa,+ kí ọ̀kan lára àwọn ọkùnrin yìí di ẹlẹ́rìí àjíǹde rẹ̀ pẹ̀lú wa.”+

23 Nítorí náà, wọ́n dábàá àwọn méjì, Jósẹ́fù tí wọ́n ń pè ní Básábà, tí wọ́n tún ń pè ní Jọ́sítù àti ẹnì kejì, Màtáyásì. 24 Wọ́n wá gbàdúrà, wọ́n sì sọ pé: “Jèhófà,* ìwọ ẹni tó mọ ọkàn gbogbo èèyàn,+ fi ẹni tí o yàn lára àwọn ọkùnrin méjì yìí hàn, 25 tó máa gba iṣẹ́ òjíṣẹ́ àti iṣẹ́ àpọ́sítélì yìí, tí Júdásì gbé sílẹ̀ kí ó lè lọ ṣe tirẹ̀.”+ 26 Nítorí náà, wọ́n ṣẹ́ kèké lé wọn,+ kèké sì mú Màtáyásì, a sì kà á mọ́* àwọn àpọ́sítélì mọ́kànlá (11).

2 Ní ọjọ́ Àjọyọ̀ Pẹ́ńtíkọ́sì,+ gbogbo wọn wà níbì kan náà, bí àjọyọ̀ náà ṣe ń lọ lọ́wọ́. 2 Lójijì, ariwo kan dún láti ọ̀run, ó dà bíi ti atẹ́gùn líle tó ń rọ́ yìì, ó sì kún gbogbo inú ilé tí wọ́n jókòó sí.+ 3 Wọ́n rí àwọn ohun tó jọ iná tó rí bí ahọ́n, wọ́n tú ká, ìkọ̀ọ̀kan sì bà lé ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn, 4 gbogbo wọn wá kún fún ẹ̀mí mímọ́,+ wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í sọ oríṣiríṣi èdè,* bí ẹ̀mí ṣe mú kí wọ́n máa sọ̀rọ̀.+

5 Nígbà yẹn, àwọn Júù olùfọkànsìn láti gbogbo orílẹ̀-èdè tó wà lábẹ́ ọ̀run wà ní Jerúsálẹ́mù.+ 6 Nígbà tí ìró yìí dún, ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn kóra jọ, wọ́n sì ń ṣe kàyéfì, torí ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn ń gbọ́ tí wọ́n ń sọ èdè rẹ̀. 7 Ní tòótọ́, ẹnu yà wọ́n gan-an, wọ́n sì sọ pé: “Ẹ wò ó, ará Gálílì+ ni gbogbo àwọn tó ń sọ̀rọ̀ yìí, àbí bẹ́ẹ̀ kọ́? 8 Báwo ló ṣe wá jẹ́ pé kálukú wa ń gbọ́ èdè ìbílẹ̀* rẹ̀? 9 Àwọn tó wà pẹ̀lú wa ni àwọn ará Pátíà, àwọn ará Mídíà+ àti àwọn ọmọ Élámù,+ àwọn tó ń gbé Mesopotámíà, Jùdíà àti Kapadókíà, Pọ́ńtù àti ìpínlẹ̀ Éṣíà,+ 10 Fíríjíà àti Panfílíà, Íjíbítì àti àwọn agbègbè Líbíà nítòsí Kírénè, àwọn àlejò láti Róòmù, àwọn Júù àti àwọn aláwọ̀ṣe,*+ 11 àwọn ará Kírétè pẹ̀lú àwọn ọmọ ilẹ̀ Arébíà, gbogbo wa gbọ́ tí wọ́n ń fi èdè wa sọ nípa àwọn ohun àgbàyanu Ọlọ́run.” 12 Àní, ẹnu ya gbogbo wọn, wọ́n sì ń ṣe kàyéfì, wọ́n ń sọ fún ara wọn pé: “Kí ni èyí túmọ̀ sí?” 13 Síbẹ̀, àwọn kan ń fi wọ́n ṣe yẹ̀yẹ́, wọ́n ń sọ pé: “Wọ́n ti mu wáìnì dídùn* yó.”

14 Àmọ́, Pétérù dìde dúró pẹ̀lú àwọn Mọ́kànlá náà,+ ó gbóhùn sókè, ó sì sọ fún wọn pé: “Ẹ̀yin èèyàn Jùdíà àti gbogbo ẹ̀yin tó ń gbé ní Jerúsálẹ́mù, ẹ jẹ́ kí ọ̀rọ̀ yìí yé yín, kí ẹ sì fara balẹ̀ gbọ́ ọ̀rọ̀ mi. 15 Ní ti tòótọ́, kì í ṣe pé àwọn èèyàn yìí mutí yó bí ẹ ṣe rò, nítorí wákàtí kẹta ọjọ́ ni.* 16 Kàkà bẹ́ẹ̀, ohun tí a gbẹnu wòlíì Jóẹ́lì sọ ni pé: 17 ‘“Ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn,” ni Ọlọ́run wí, “èmi yóò tú lára ẹ̀mí mi sára onírúurú èèyàn,* àwọn ọmọ yín lọ́kùnrin àti lóbìnrin yóò máa sọ tẹ́lẹ̀, àwọn ọ̀dọ́kùnrin yín yóò máa rí ìran, àwọn àgbà ọkùnrin yín yóò sì máa lá àlá,+ 18 kódà, èmi yóò tú lára ẹ̀mí mi sára àwọn ẹrúkùnrin mi àti sára àwọn ẹrúbìnrin mi ní àwọn ọjọ́ náà, wọ́n á sì máa sọ tẹ́lẹ̀.+ 19 Èmi yóò fi àwọn ohun ìyanu* hàn ní ọ̀run lókè àti àwọn iṣẹ́ àmì ní ayé nísàlẹ̀, ẹ̀jẹ̀ àti iná pẹ̀lú èéfín tó ṣú bolẹ̀. 20 Oòrùn yóò ṣókùnkùn, òṣùpá yóò sì di ẹ̀jẹ̀, kí ọjọ́ ńlá àti ọjọ́ olókìkí Jèhófà* tó dé. 21 Gbogbo ẹni tó bá ń ké pe orúkọ Jèhófà* yóò sì rí ìgbàlà.”’+

22 “Ẹ̀yin èèyàn Ísírẹ́lì, ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ yìí: Jésù ará Násárẹ́tì ni ọkùnrin tí Ọlọ́run fi hàn yín ní gbangba nípasẹ̀ àwọn iṣẹ́ agbára àti àwọn ohun ìyanu* pẹ̀lú àwọn iṣẹ́ àmì tí Ọlọ́run ṣe nípasẹ̀ rẹ̀ láàárín yín,+ bí ẹ̀yin fúnra yín ṣe mọ̀. 23 Ọkùnrin yìí, tí a fà lé yín lọ́wọ́ nípasẹ̀ ìpinnu* àti ìmọ̀ Ọlọ́run,+ ni ẹ ti ọwọ́ àwọn arúfin kàn mọ́gi,* tí ẹ sì pa.+ 24 Àmọ́ Ọlọ́run jí i dìde,+ bó ṣe gbà á sílẹ̀ lọ́wọ́ oró* ikú, torí ikú ò lè dì í mú títí lọ.+ 25 Dáfídì sọ nípa rẹ̀ pé: ‘Mo gbé Jèhófà* síwájú mi nígbà gbogbo, ó wà ní ọwọ́ ọ̀tún mi, kí mìmì kan má bàa mì mí. 26 Nítorí èyí, ara mi yá gágá, ahọ́n mi sì ń yọ̀ gidigidi. Màá* sì máa fi ìrètí gbé ayé; 27 torí o ò ní fi mí* sílẹ̀ nínú Isà Òkú,* bẹ́ẹ̀ ni o ò ní jẹ́ kí ẹni ìdúróṣinṣin rẹ rí ìdíbàjẹ́.+ 28 O ti jẹ́ kí n mọ ọ̀nà ìyè; wàá mú kí ayọ̀ púpọ̀ kún ọkàn mi níwájú rẹ.’+

29 “Ẹ̀yin èèyàn, ẹ̀yin ará, ẹ jẹ́ kí n sọ̀rọ̀ ní fàlàlà fún yín nípa Dáfídì, olórí ìdílé, pé ó kú, wọ́n sin ín,+ ibojì rẹ̀ sì wà lọ́dọ̀ wa títí di òní yìí. 30 Nítorí pé wòlíì ni, ó sì mọ̀ pé Ọlọ́run ti búra fún òun pé òun máa gbé ọ̀kan lára àwọn ọmọ rẹ̀* gorí ìtẹ́ rẹ̀,+ 31 ó ti rí i tẹ́lẹ̀, ó sì sọ nípa àjíǹde Kristi, pé a kò fi í sílẹ̀ nínú Isà Òkú,* bẹ́ẹ̀ ni ara rẹ̀ kò rí ìdíbàjẹ́.*+ 32 Ọlọ́run jí Jésù yìí dìde, gbogbo wa sì jẹ́rìí sí i.+ 33 Tóò, nítorí pé a gbé e ga sí ọwọ́ ọ̀tún Ọlọ́run,+ tí ó sì gba ẹ̀mí mímọ́ tí Baba ṣèlérí,+ ó tú ohun tí ẹ rí, tí ẹ sì gbọ́ jáde. 34 Nítorí Dáfídì kò lọ sí ọ̀run, àmọ́ òun fúnra rẹ̀ sọ pé, ‘Jèhófà* sọ fún Olúwa mi pé: “Jókòó sí ọwọ́ ọ̀tún mi 35 títí màá fi fi àwọn ọ̀tá rẹ ṣe àpótí ìtìsẹ̀ rẹ.”’+ 36 Nítorí náà, kí gbogbo ilé Ísírẹ́lì mọ̀ dájú pé, Jésù yìí tí ẹ kàn mọ́gi*+ ni Ọlọ́run fi ṣe Olúwa+ àti Kristi.”

37 Nígbà tí wọ́n gbọ́ ọ̀rọ̀ yìí, ó gún wọn dé ọkàn, wọ́n sì sọ fún Pétérù àti àwọn àpọ́sítélì yòókù pé: “Ẹ̀yin èèyàn, ẹ̀yin ará, kí ni ká ṣe?” 38 Pétérù sọ fún wọn pé: “Ẹ ronú pìwà dà,+ kí a sì batisí ẹnì kọ̀ọ̀kan yín+ ní orúkọ Jésù Kristi, kí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ yín lè ní ìdáríjì,+ ẹ ó sì gba ẹ̀bùn ọ̀fẹ́ ẹ̀mí mímọ́. 39 Nítorí ìlérí náà+ wà fún ẹ̀yin pẹ̀lú àwọn ọmọ yín àti fún gbogbo àwọn tó wà lọ́nà jíjìn, fún gbogbo àwọn tí Jèhófà* Ọlọ́run wa bá pè wá sọ́dọ̀ ara rẹ̀.”+ 40 Ó tún bá wọn sọ ọ̀rọ̀ púpọ̀, ó jẹ́rìí kúnnákúnná, ó sì ń gbà wọ́n níyànjú, pé: “Ẹ gba ara yín lọ́wọ́ ìran oníbékebèke yìí.”+ 41 Nítorí náà, àwọn tó fi ayọ̀ gba ọ̀rọ̀ rẹ̀ ṣe ìrìbọmi,+ ní ọjọ́ yẹn nǹkan bí ẹgbẹ̀rún mẹ́ta (3,000) èèyàn* ló dara pọ̀ mọ́ wọn.+ 42 Wọ́n ń tẹra mọ́ ẹ̀kọ́ àwọn àpọ́sítélì, wọ́n ń wà pa pọ̀,* wọ́n ń jẹun,+ wọ́n sì ń gbàdúrà.+

43 Ní tòótọ́, ẹ̀rù bẹ̀rẹ̀ sí í ba gbogbo èèyàn,* ọ̀pọ̀ ohun ìyanu* àti iṣẹ́ àmì sì bẹ̀rẹ̀ sí í ṣẹlẹ̀ látọwọ́ àwọn àpọ́sítélì.+ 44 Gbogbo àwọn tó di onígbàgbọ́ wà pa pọ̀, wọ́n sì jọ ń lo gbogbo ohun tí wọ́n ní, 45 wọ́n ń ta àwọn ohun ìní+ àti dúkìá wọn, wọ́n sì ń pín owó tí wọ́n rí níbẹ̀ fún gbogbo wọn, bí ohun tí ẹnì kọ̀ọ̀kan nílò bá ṣe pọ̀ tó.+ 46 Láti ọjọ́ dé ọjọ́, wọ́n ń pésẹ̀ déédéé sí tẹ́ńpìlì pẹ̀lú èrò tó ṣọ̀kan, wọ́n ń jẹun ní ilé ara wọn, wọ́n sì ń fi ayọ̀ púpọ̀ àti òótọ́ ọkàn pín oúnjẹ fún ara wọn, 47 wọ́n ń yin Ọlọ́run, wọ́n sì ń rí ojú rere lọ́dọ̀ gbogbo èèyàn. Lẹ́sẹ̀ kan náà, Jèhófà* ń mú kí àwọn tó ń rí ìgbàlà dara pọ̀ mọ́ wọn lójoojúmọ́.+

3 Nígbà kan, Pétérù àti Jòhánù ń lọ sí tẹ́ńpìlì lákòókò àdúrà, ní wákàtí kẹsàn-án,* 2 àwọn kan sì ń gbé ọkùnrin kan tó ti yarọ láti ìgbà tí wọ́n ti bí i kọjá. Ojoojúmọ́ ni wọ́n máa ń gbé e sí tòsí ẹnu ilẹ̀kùn tẹ́ńpìlì tí wọ́n ń pè ní Ẹlẹ́wà, kó lè máa gba ọrẹ àánú lọ́wọ́ àwọn tó ń wọ tẹ́ńpìlì. 3 Nígbà tí ọkùnrin náà tajú kán rí Pétérù àti Jòhánù tí wọ́n fẹ́ wọ tẹ́ńpìlì, ó bẹ̀rẹ̀ sí í béèrè ọrẹ àánú lọ́wọ́ wọn. 4 Àmọ́, Pétérù àti Jòhánù tẹjú mọ́ ọn, wọ́n sì sọ pé: “Wò wá.” 5 Ló bá ń wò wọ́n, ó sì ń retí pé òun máa rí nǹkan gbà lọ́wọ́ wọn. 6 Àmọ́ Pétérù sọ pé: “Mi ò ní fàdákà àti wúrà, àmọ́ ohun tí mo ní ni màá fún ọ. Ní orúkọ Jésù Kristi ará Násárẹ́tì, máa rìn!”+ 7 Ló bá di ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ mú, ó sì gbé e dìde.+ Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, ẹsẹ̀ rẹ̀ àti ọrùn ẹsẹ̀ rẹ̀ le gírígírí;+ 8 ó fò sókè,+ ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í rìn, ó tẹ̀ lé wọn wọ tẹ́ńpìlì, ó ń rìn, ó ń fò sókè, ó sì ń yin Ọlọ́run. 9 Gbogbo èèyàn sì rí i tó ń rìn, tó sì ń yin Ọlọ́run. 10 Wọ́n dá a mọ̀ pé òun ni ọkùnrin tó máa ń jókòó síbi Ẹnubodè Ẹlẹ́wà tó wà ní tẹ́ńpìlì+ láti máa gba ọrẹ àánú, ẹnu yà wọ́n gidigidi, ohun tó ṣẹlẹ̀ sí i sì múnú wọn dùn gan-an.

11 Nígbà tí ọkùnrin náà ṣì di Pétérù àti Jòhánù mú, gbogbo èèyàn sáré lọ bá wọn níbi tí wọ́n ń pè ní Ọ̀dẹ̀dẹ̀* Sólómọ́nì,+ ẹnu yà wọ́n gidigidi. 12 Nígbà tí Pétérù rí ohun tó ṣẹlẹ̀, ọ́ sọ fún àwọn èèyàn náà pé: “Ẹ̀yin èèyàn Ísírẹ́lì, kí ló dé tọ́rọ̀ yìí fi ń yà yín lẹ́nu? Kí ló dé tí ẹ fi ń wò wá bíi pé agbára wa ló tó bẹ́ẹ̀, àbí torí pé ìfọkànsin Ọlọ́run tí a ní la fi mú kí ọkùnrin yìí máa rìn? 13 Ọlọ́run Ábúráhámù àti ti Ísákì àti ti Jékọ́bù,+ Ọlọ́run àwọn baba ńlá wa, ti ṣe Jésù,+ Ìránṣẹ́ rẹ̀ lógo,+ ẹni tí ẹ fà lé àwọn èèyàn lọ́wọ́,+ tí ẹ sì sọ níwájú Pílátù pé ẹ ò mọ̀ rí, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ti pinnu pé òun máa dá a sílẹ̀. 14 Bẹ́ẹ̀ ni, ẹ sọ pé ẹ ò mọ ẹni mímọ́ àti olódodo yẹn rí, ẹ sì ní kí wọ́n fún yín ní ọkùnrin tó jẹ́ apààyàn,+ 15 ẹ wá pa Olórí Aṣojú ìyè.+ Àmọ́ Ọlọ́run gbé e dìde kúrò nínú ikú, òtítọ́ yìí ni àwa ń jẹ́rìí sí.+ 16 Nípasẹ̀ orúkọ rẹ̀ àti nípa ìgbàgbọ́ tí a ní nínú orúkọ rẹ̀, ni ara ọkùnrin tí ẹ rí, tí ẹ sì mọ̀ yìí fi yá. Ìgbàgbọ́ tí a ní nípasẹ̀ rẹ̀ ló mú ara ọkùnrin yìí dá ṣáṣá níṣojú gbogbo yín. 17 Ní báyìí, ẹ̀yin ará, mo mọ̀ pé àìmọ̀kan ló sún yín ṣe é,+ bí àwọn alákòóso yín náà ti ṣe.+ 18 Àmọ́ ọ̀nà yìí ni Ọlọ́run gbà mú àwọn ohun tó ti kéde tẹ́lẹ̀ látẹnu gbogbo àwọn wòlíì ṣẹ, pé Kristi òun máa jìyà.+

19 “Nítorí náà, ẹ ronú pìwà dà,+ kí ẹ sì yí pa dà,+ kí Ọlọ́run lè pa àwọn ẹ̀ṣẹ̀ yín rẹ́,+ kí àwọn àsìkò ìtura lè wá látọ̀dọ̀ Jèhófà fúnra rẹ̀,* 20 kí ó sì lè rán Kristi tí ó ti yàn nítorí yín, ìyẹn Jésù. 21 Ọ̀run gbọ́dọ̀ gba ẹni yìí sínú ara rẹ̀ títí di àwọn àkókò ìmúbọ̀sípò gbogbo ohun tí Ọlọ́run sọ látẹnu àwọn wòlíì rẹ̀ mímọ́ ti ìgbà àtijọ́. 22 Kódà, Mósè sọ pé: ‘Jèhófà* Ọlọ́run yín máa gbé wòlíì kan bí èmi dìde fún yín láàárín àwọn arákùnrin yín.+ Ẹ gbọ́dọ̀ fetí sí ohun tó bá sọ fún yín.+ 23 Ní tòótọ́, ẹni* tí kò bá fetí sí Wòlíì yẹn ni a ó pa run pátápátá kúrò láàárín àwọn èèyàn.’+ 24 Gbogbo àwọn wòlíì, látorí Sámúẹ́lì àti àwọn tó tẹ̀ lé e, gbogbo wọn ti sọ̀rọ̀, wọ́n sì kéde àwọn ọjọ́ yìí lọ́nà tó ṣe kedere.+ 25 Ẹ̀yin ni ọmọ àwọn wòlíì àti ti májẹ̀mú tí Ọlọ́run bá àwọn baba ńlá yín dá,+ tí ó sọ fún Ábúráhámù pé: ‘Gbogbo ìdílé tó wà láyé yóò rí ìbùkún nípasẹ̀ ọmọ* rẹ.’+ 26 Ẹ̀yin ni Ọlọ́run kọ́kọ́ rán Ìránṣẹ́ rẹ̀ sí,+ lẹ́yìn tí ó gbé e dìde, kí ó lè bù kún yín láti mú kí ẹnì kọ̀ọ̀kan yín yí pa dà kúrò nínú àwọn iṣẹ́ ibi rẹ̀.”

4 Nígbà tí àwọn méjèèjì ń bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀ lọ́wọ́, àwọn àlùfáà, olórí ẹ̀ṣọ́ tẹ́ńpìlì àti àwọn Sadusí+ wá bá wọn. 2 Inú ń bí wọn torí pé àwọn àpọ́sítélì ń kọ́ àwọn èèyàn, wọ́n sì ń kéde ní gbangba nípa àjíǹde Jésù kúrò nínú ikú.*+ 3 Torí náà, wọ́n gbá wọn mú,* wọ́n sì fi wọ́n sínú àhámọ́+ títí di ọjọ́ kejì, nítorí ilẹ̀ ti ń ṣú. 4 Síbẹ̀, ọ̀pọ̀ lára àwọn tó gbọ́ ọ̀rọ̀ wọn di onígbàgbọ́, iye àwọn ọkùnrin náà sì di nǹkan bí ẹgbẹ̀rún márùn-ún (5,000).+

5 Lọ́jọ́ kejì, àwọn alákòóso wọn, àwọn àgbààgbà àti àwọn akọ̀wé òfin kóra jọ ní Jerúsálẹ́mù, 6 pẹ̀lú Ánásì+ olórí àlùfáà, Káyáfà,+ Jòhánù, Alẹkisáńdà àti gbogbo mọ̀lẹ́bí olórí àlùfáà. 7 Wọ́n ní kí Pétérù àti Jòhánù dúró ní àárín wọn, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í da ìbéèrè bò wọ́n, wọ́n ní: “Agbára wo tàbí orúkọ ta ni ẹ fi ṣe èyí?” 8 Ni Pétérù, tí ó ti kún fún ẹ̀mí mímọ́,+ bá sọ fún wọn pé:

“Ẹ̀yin alákòóso àti ẹ̀yin àgbààgbà, 9 tó bá jẹ́ pé lórí oore tí a ṣe fún ọkùnrin tó yarọ + ni ẹ ṣe ń wádìí lónìí yìí, tí ẹ sì fẹ́ mọ ẹni tó mú ọkùnrin yìí lára dá, 10 kí gbogbo yín àti gbogbo èèyàn Ísírẹ́lì yáa mọ̀ pé ní orúkọ Jésù Kristi ará Násárẹ́tì,+ ẹni tí ẹ kàn mọ́gi,*+ àmọ́ tí Ọlọ́run gbé dìde kúrò nínú ikú,+ ni ọkùnrin yìí fi dúró níbí pẹ̀lú ara yíyá gágá níwájú yín. 11 Jésù yìí ni ‘òkúta tí ẹ̀yin kọ́lékọ́lé ò kà sí tó ti wá di olórí òkúta igun ilé.’*+ 12 Yàtọ̀ síyẹn, kò sí ìgbàlà lọ́dọ̀ ẹlòmíì, nítorí kò sí orúkọ míì+ lábẹ́ ọ̀run tí a fún àwọn èèyàn tí a lè tipasẹ̀ rẹ̀ rí ìgbàlà.”+

13 Nígbà tí wọ́n rí bí ọ̀rọ̀ ṣe dá lẹ́nu Pétérù àti Jòhánù,* tí wọ́n sì mọ̀ pé wọn ò kàwé* àti pé wọ́n jẹ́ gbáàtúù,+ ẹnu yà wọ́n gan-an. Wọ́n wá rántí pé wọ́n ti máa ń wà pẹ̀lú Jésù.+ 14 Bí wọ́n ṣe ń wo ọkùnrin tí a ti wò sàn tó dúró pẹ̀lú wọn,+ wọn ò lè fèsì kankan sí ọ̀rọ̀ náà.+ 15 Torí náà, wọ́n pàṣẹ fún wọn pé kí wọ́n jáde síta gbọ̀ngàn Sàhẹ́ndìrìn, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í fikùn lukùn, 16 wọ́n sọ pé: “Kí ni ká ṣe sọ́rọ̀ àwọn ọkùnrin yìí?+ Nítorí, ká sòótọ́, wọ́n ti ṣe iṣẹ́ àmì tó gbàfiyèsí, ó sì ṣe kedere sí gbogbo àwọn tó ń gbé Jerúsálẹ́mù,+ a ò sì lè sọ pé kò ṣẹlẹ̀. 17 Kí ọ̀rọ̀ yìí má bàa tàn kọjá ibi tó dé láàárín àwọn èèyàn, ẹ jẹ́ ká halẹ̀ mọ́ wọn, ká sì sọ fún wọn pé wọn ò tún gbọ́dọ̀ sọ nípa orúkọ yìí fún ẹnikẹ́ni mọ́.”+

18 Ni wọ́n bá pè wọ́n, wọ́n sì pàṣẹ fún wọn pé kí wọ́n má ṣe sọ ohunkóhun tàbí kọ́ni nípa orúkọ Jésù mọ́. 19 Àmọ́, Pétérù àti Jòhánù fún wọn lésì pé: “Ẹ̀yin náà ẹ sọ, tó bá tọ́ lójú Ọlọ́run pé ká fetí sí yín dípò ká fetí sí Ọlọ́run. 20 Àmọ́ ní tiwa, a ò lè ṣàì sọ ohun tí a ti rí tí a sì ti gbọ́.”+ 21 Torí náà, lẹ́yìn tí wọ́n ti halẹ̀ mọ́ wọn sí i, wọ́n dá wọn sílẹ̀, torí wọn ò rí ìdí tí wọ́n á fi fìyà jẹ wọ́n, wọ́n sì tún ro ti àwọn èèyàn náà,+ torí ńṣe ni gbogbo wọn ń yin Ọlọ́run lógo lórí ohun tó ti ṣẹlẹ̀. 22 Nítorí ọkùnrin tí wọ́n fi iṣẹ́ ìyanu* wò sàn yìí ti lé lẹ́ni ogójì (40) ọdún.

23 Lẹ́yìn tí wọ́n dá wọn sílẹ̀, wọ́n lọ bá àwọn èèyàn wọn, wọ́n sì ròyìn ohun tí àwọn olórí àlùfáà àti àwọn àgbààgbà sọ fún wọn. 24 Nígbà tí wọ́n gbọ́, gbogbo wọn jọ gbé ohùn wọn sókè sí Ọlọ́run, wọ́n sọ pé:

“Olúwa Ọba Aláṣẹ, ìwọ ni Ẹni tó dá ọ̀run àti ayé àti òkun pẹ̀lú gbogbo ohun tó wà nínú wọn,+ 25 tó sì tipasẹ̀ ẹ̀mí mímọ́ gbẹnu Dáfídì+ baba ńlá wa tó jẹ́ ìránṣẹ́ rẹ sọ pé: ‘Kí nìdí tí àwọn orílẹ̀-èdè fi ń ṣe awuyewuye, tí àwọn èèyàn sì ń ṣe àṣàrò lórí ohun asán? 26 Àwọn ọba ayé dúró, àwọn alákòóso sì kóra jọ láti dojú kọ Jèhófà* àti ẹni àmì òróró* rẹ̀.’+ 27 Ní tòótọ́, Hẹ́rọ́dù àti Pọ́ńtíù Pílátù+ pẹ̀lú àwọn èèyàn àwọn orílẹ̀-èdè àti àwọn èèyàn Ísírẹ́lì kóra jọ ní ìlú yìí láti dojú kọ Jésù, ìránṣẹ́ rẹ mímọ́, ẹni tí o fòróró yàn,+ 28 kí wọ́n lè ṣe àwọn ohun tí o ti pinnu nípasẹ̀ ọwọ́ rẹ àti ìmọ̀ràn rẹ pé kó ṣẹlẹ̀.+ 29 Ní báyìí, Jèhófà,* fiyè sí ìhàlẹ̀ wọn, kí o sì jẹ́ kí àwa ẹrú rẹ máa sọ ọ̀rọ̀ rẹ nìṣó pẹ̀lú ìgboyà, 30 bí o ṣe ń na ọwọ́ rẹ jáde láti múni lára dá, tí àwọn iṣẹ́ àmì àti iṣẹ́ ìyanu* sì ń ṣẹlẹ̀+ nípasẹ̀ orúkọ Jésù ìránṣẹ́ rẹ mímọ́.”+

31 Nígbà tí wọ́n rawọ́ ẹ̀bẹ̀* tán, ibi tí wọ́n kóra jọ sí mì tìtì, gbogbo wọn lẹ́nì kọ̀ọ̀kan kún fún ẹ̀mí mímọ́,+ wọ́n sì ń fi ìgboyà sọ̀rọ̀ Ọlọ́run.+

32 Yàtọ̀ síyẹn, ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn tó di onígbàgbọ́ wá ṣọ̀kan ní inú* àti ọkàn, kódà kò sí ìkankan nínú wọn tó sọ pé ohun tí òun ní jẹ́ tòun, ṣe ni wọ́n jọ ń lo gbogbo ohun tí wọ́n ní.+ 33 Pẹ̀lú agbára ńlá, àwọn àpọ́sítélì ń jẹ́rìí nìṣó nípa àjíǹde Jésù Olúwa,+ inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí sì wà lórí gbogbo wọn lọ́pọ̀lọpọ̀. 34 Ní ti tòótọ́, kò sẹ́ni tó ṣaláìní láàárín wọn,+ torí ṣe ni gbogbo àwọn tó ní ilẹ̀ tàbí ilé ń tà wọ́n, tí wọ́n sì ń mú owó ohun tí wọ́n tà wá, 35 wọ́n á sì fi sílẹ̀ lẹ́gbẹ̀ẹ́ ẹsẹ̀ àwọn àpọ́sítélì.+ Àwọn náà á wá pín in fún ẹnì kọ̀ọ̀kan bí ohun tó nílò bá ṣe pọ̀ tó.+ 36 Nítorí náà, Jósẹ́fù, tí àwọn àpọ́sítélì tún ń pè ní Bánábà+ (tó túmọ̀ sí “Ọmọ Ìtùnú”, nígbà tí a bá túmọ̀ rẹ̀), tó jẹ́ ọmọ Léfì, ọmọ ìbílẹ̀ Sápírọ́sì, 37 ní ilẹ̀ kan, ó tà á, ó sì mú owó náà wá, ó sì fi sílẹ̀ lẹ́gbẹ̀ẹ́ ẹsẹ̀ àwọn àpọ́sítélì.+

5 Ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Ananáyà pẹ̀lú Sàfírà ìyàwó rẹ̀ ta àwọn ohun ìní kan. 2 Àmọ́, ó yọ lára owó náà pa mọ́, ìyàwó rẹ̀ sì mọ̀ sí i, ó wá mú apá kan rẹ̀ wá, ó sì fi í sílẹ̀ lẹ́gbẹ̀ẹ́ ẹsẹ̀ àwọn àpọ́sítélì.+ 3 Àmọ́ Pétérù sọ pé: “Ananáyà, kí ló dé tí Sátánì fi kì ọ́ láyà láti parọ́ + fún ẹ̀mí mímọ́,+ tí o fi yọ lára owó ilẹ̀ náà pa mọ́? 4 Ní gbogbo ìgbà tó wà lọ́wọ́ rẹ, ṣé kì í ṣe tìrẹ ni? Lẹ́yìn tí o sì tà á, ṣé kì í ṣe ìkáwọ́ rẹ ló wà ni? Kí ló dé tí o fi ro irú nǹkan yìí lọ́kàn rẹ? Èèyàn kọ́ lo parọ́ fún, Ọlọ́run ni.” 5 Bí Ananáyà ṣe gbọ́ ọ̀rọ̀ yìí, ó ṣubú lulẹ̀, ó sì kú. Jìnnìjìnnì sì bo gbogbo àwọn tó gbọ́ nípa rẹ̀. 6 Àwọn ọ̀dọ́kùnrin bá dìde, wọ́n fi aṣọ wé e, wọ́n gbé e jáde, wọ́n sì sin ín.

7 Lẹ́yìn nǹkan bíi wákàtí mẹ́ta, ìyàwó rẹ̀ wọlé, àmọ́ kò mọ ohun tó ṣẹlẹ̀. 8 Pétérù sọ fún un pé: “Sọ fún mi, ṣé iye tí ẹ̀yin méjèèjì ta ilẹ̀ náà nìyí?” Ó sọ pé: “Bẹ́ẹ̀ ni, iye rẹ̀ nìyẹn.” 9 Ni Pétérù bá sọ fún un pé: “Kí ló dé tí ẹ̀yin méjèèjì fi fohùn ṣọ̀kan láti dán ẹ̀mí Jèhófà* wò? Wò ó! Àwọn tó lọ sin ọkọ rẹ ti wà lẹ́nu ọ̀nà, wọ́n á gbé ìwọ náà jáde.” 10 Lójú ẹsẹ̀, ó ṣubú lulẹ̀ lẹ́gbẹ̀ẹ́ ẹsẹ̀ Pétérù, ó sì kú. Nígbà tí àwọn ọ̀dọ́kùnrin náà wọlé, wọ́n bá a tí ó ti kú, wọ́n gbé e jáde, wọ́n sì sin ín sí ẹ̀gbẹ́ ọkọ rẹ̀. 11 Jìnnìjìnnì wá bo gbogbo ìjọ àti gbogbo àwọn tó gbọ́ nípa nǹkan yìí.

12 Yàtọ̀ síyẹn, ọ̀pọ̀ iṣẹ́ àmì àti iṣẹ́ ìyanu* ló ń ṣẹlẹ̀ látọwọ́ àwọn àpọ́sítélì láàárín àwọn èèyàn;+ gbogbo wọn sì máa ń pé jọ nínú Ọ̀dẹ̀dẹ̀* Sólómọ́nì.+ 13 Àmọ́, àwọn míì ò láyà láti dara pọ̀ mọ́ wọn; síbẹ̀, àwọn èèyàn ń sọ̀rọ̀ wọn dáadáa. 14 Ju gbogbo rẹ̀ lọ, ṣe ni àwọn onígbàgbọ́ nínú Olúwa ń dara pọ̀ mọ́ wọn, iye wọn sì pọ̀ lọ́kùnrin àti lóbìnrin.+ 15 Kódà, wọ́n ń gbé àwọn aláìsàn wá sí àwọn ojú ọ̀nà, wọ́n á tẹ́ wọn síbẹ̀ lórí àwọn ibùsùn kéékèèké àti ẹní, kí ó lè jẹ́ pé tí Pétérù bá ń kọjá, ó kéré tán, òjìji rẹ̀ á kọjá lára àwọn kan nínú wọn.+ 16 Bákan náà, ọ̀pọ̀ èèyàn ń wá láti àwọn ìlú tó wà ní àyíká Jerúsálẹ́mù, wọ́n ń gbé àwọn aláìsàn àti àwọn tí àwọn ẹ̀mí àìmọ́ ń dà láàmú wá, gbogbo wọn sì ń rí ìwòsàn lẹ́nì kọ̀ọ̀kan.

17 Àmọ́ àlùfáà àgbà dìde àti gbogbo àwọn tó wà pẹ̀lú rẹ̀, tí wọ́n wà nínú ẹ̀ya ìsìn àwọn Sadusí, inú bí wọn* gidigidi. 18 Wọ́n gbá àwọn àpọ́sítélì mú,* wọ́n sì tì wọ́n mọ́ inú ẹ̀wọ̀n ìlú.+ 19 Àmọ́ ní òru, áńgẹ́lì Jèhófà* ṣí àwọn ilẹ̀kùn ẹ̀wọ̀n náà,+ ó mú wọn jáde, ó sì sọ pé: 20 “Ẹ lọ dúró sínú tẹ́ńpìlì, kí ẹ sì máa sọ gbogbo ọ̀rọ̀ ìyè yìí fún àwọn èèyàn.” 21 Lẹ́yìn tí wọ́n gbọ́ ọ̀rọ̀ yìí, wọ́n wọ tẹ́ńpìlì ní àfẹ̀mọ́jú, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ni.

Nígbà tí àlùfáà àgbà àti àwọn tó wà pẹ̀lú rẹ̀ dé, wọ́n pe Sàhẹ́ndìrìn àti gbogbo àpéjọ àgbààgbà àwọn ọmọ Ísírẹ́lì jọ, wọ́n sì ní kí wọ́n lọ mú àwọn àpọ́sítélì wá látinú ẹ̀wọ̀n. 22 Àmọ́ nígbà tí àwọn ẹ̀ṣọ́ dé ibẹ̀, wọn ò rí wọn nínú ẹ̀wọ̀n. Torí náà, wọ́n pa dà wá ròyìn, 23 wọ́n ní: “A bá ẹ̀wọ̀n ní títì pa, àwọn ẹ̀ṣọ́ dúró lẹ́nu àwọn ilẹ̀kùn, àmọ́ nígbà tí a ṣílẹ̀kùn, a ò rí ẹnì kankan níbẹ̀.” 24 Tóò, nígbà tí olórí ẹ̀ṣọ́ tẹ́ńpìlì àti àwọn olórí àlùfáà gbọ́ ọ̀rọ̀ yìí, ọkàn wọn dà rú torí wọn ò mọ ohun tí èyí máa yọrí sí. 25 Àmọ́ ẹnì kan wá, ó sì sọ fún wọn pé: “Ẹ wò ó! Àwọn ọkùnrin tí ẹ fi sẹ́wọ̀n wà nínú tẹ́ńpìlì, wọ́n dúró, wọ́n sì ń kọ́ àwọn èèyàn.” 26 Ni olórí ẹ̀ṣọ́ bá lọ pẹ̀lú àwọn ẹ̀ṣọ́ rẹ̀, ó sì mú àwọn àpọ́sítélì wọlé, àmọ́ kì í ṣe tipátipá, torí wọ́n ń bẹ̀rù kí àwọn èèyàn má lọ sọ wọ́n lókùúta.+

27 Torí náà, wọ́n mú wọn wá, wọ́n sì ní kí wọ́n dúró níwájú Sàhẹ́ndìrìn. Àlùfáà àgbà wá bi wọ́n ní ìbéèrè, 28 ó sì sọ pé: “A kìlọ̀ fún yín gidigidi pé kí ẹ má ṣe máa kọ́ni nípa orúkọ yìí,+ síbẹ̀, ẹ wò ó! ẹ ti fi ẹ̀kọ́ yín kún Jerúsálẹ́mù, ẹ sì pinnu láti mú ẹ̀jẹ̀ ọkùnrin yìí wá sórí wa.”+ 29 Pétérù àti àwọn àpọ́sítélì yòókù wá fún wọn lésì pé: “A gbọ́dọ̀ ṣègbọràn sí Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí alákòóso dípò èèyàn.+ 30 Ọlọ́run àwọn baba ńlá wa gbé Jésù dìde, ẹni tí ẹ pa, tí ẹ sì gbé kọ́ òpó igi.*+ 31 Ọlọ́run gbé ẹni yìí ga sí ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀+ láti jẹ́ Olórí Aṣojú+ àti Olùgbàlà,+ kí ó lè mú kí Ísírẹ́lì ronú pìwà dà, kí wọ́n sì rí ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ gbà.+ 32 Àwa ni ẹlẹ́rìí àwọn nǹkan yìí,+ bẹ́ẹ̀ sì ni ẹ̀mí mímọ́,+ èyí tí Ọlọ́run fún àwọn tó ń ṣègbọràn sí i gẹ́gẹ́ bí alákòóso.”

33 Nígbà tí wọ́n gbọ́ èyí, wọ́n gbaná jẹ,* wọ́n sì fẹ́ pa wọ́n dà nù. 34 Àmọ́ Farisí kan tó ń jẹ́ Gàmálíẹ́lì + dìde nínú Sàhẹ́ndìrìn; olùkọ́ Òfin tí gbogbo èèyàn kà sí ni, ó sì pàṣẹ pé kí wọ́n mú àwọn ọkùnrin náà lọ síta fúngbà díẹ̀. 35 Ó wá sọ fún wọn pé: “Ẹ̀yin èèyàn Ísírẹ́lì, ẹ ro ohun tí ẹ fẹ́ ṣe sí àwọn ọkùnrin yìí dáadáa o. 36 Bí àpẹẹrẹ, ní ìjelòó, Téúdásì dìde, ó sọ pé èèyàn pàtàkì ni òun, àwọn bí ọgọ́rùn-ún mẹ́rin (400) èèyàn sì dara pọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ rẹ̀. Àmọ́ wọ́n pa á dà nù, gbogbo àwọn tó ń tẹ̀ lé e tú ká, wọ́n sì dàwátì. 37 Lẹ́yìn rẹ̀, Júdásì ará Gálílì dìde ní àkókò ìforúkọsílẹ̀, ó sì fa àwọn èèyàn sẹ́yìn ara rẹ̀. Ọkùnrin yẹn náà ṣègbé, gbogbo àwọn tó ń tẹ̀ lé e sì tú ká. 38 Nítorí náà, níbi tọ́rọ̀ dé yìí, màá sọ fún yín pé kí ẹ má tojú bọ ọ̀rọ̀ àwọn ọkùnrin yìí, ẹ fi wọ́n sílẹ̀. Torí tó bá jẹ́ pé ọ̀dọ̀ èèyàn ni ète tàbí iṣẹ́ yìí ti wá, a ó bì í ṣubú; 39 àmọ́ tó bá jẹ́ pé ọ̀dọ̀ Ọlọ́run ni, ẹ ò ní lè bì wọ́n ṣubú.+ Àìjẹ́ bẹ́ẹ̀, ẹ̀ẹ́ kàn rí i pé ẹ̀ ń bá Ọlọ́run jà ni.”+ 40 Ni wọ́n bá gba ìmọ̀ràn rẹ̀, wọ́n sì pe àwọn àpọ́sítélì, wọ́n nà wọ́n lẹ́gba,*+ wọ́n sì pàṣẹ fún wọn pé kí wọ́n má sọ̀rọ̀ nípa orúkọ Jésù mọ́, wọ́n wá fi wọ́n sílẹ̀.

41 Torí náà, wọ́n jáde kúrò níwájú Sàhẹ́ndìrìn, wọ́n ń yọ̀+ nítorí a ti kà wọ́n yẹ láti jìyà nítorí orúkọ Jésù. 42 Lójoojúmọ́ nínú tẹ́ńpìlì àti láti ilé dé ilé,+ wọ́n ń kọ́ni láìdábọ̀, wọ́n sì ń kéde ìhìn rere nípa Kristi náà, Jésù.+

6 Lákòókò yẹn, bí àwọn ọmọ ẹ̀yìn ṣe ń pọ̀ sí i, àwọn Júù tó ń sọ èdè Gíríìkì bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàròyé nípa àwọn Júù tó ń sọ èdè Hébérù, nítorí pé àwọn tó ń pín nǹkan lójoojúmọ́ ń gbójú fo àwọn opó wọn.+ 2 Ni àwọn Méjìlá náà bá pe ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọmọ ẹ̀yìn jọ, wọ́n sì sọ pé: “Kò tọ́ kí a* fi ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sílẹ̀ ká wá máa pín oúnjẹ sórí tábìlì.+ 3 Nítorí náà, ẹ̀yin ará, ẹ yan àwọn ọkùnrin méje láàárín yín tí wọ́n lórúkọ rere,*+ tí wọ́n kún fún ẹ̀mí àti ọgbọ́n,+ kí a lè yàn wọ́n láti máa bójú tó ọ̀ràn tó pọn dandan yìí;+ 4 àmọ́, àwa á gbájú mọ́ àdúrà àti iṣẹ́ òjíṣẹ́ ọ̀rọ̀ náà.” 5 Ohun tí wọ́n sọ dùn mọ́ gbogbo àwọn èèyàn náà nínú, wọ́n sì yan Sítéfánù, ọkùnrin tó kún fún ìgbàgbọ́ àti ẹ̀mí mímọ́ pẹ̀lú Fílípì,+ Pírókórọ́sì, Níkánọ̀, Tímónì, Páménásì àti Níkóláósì tó jẹ́ aláwọ̀ṣe* ará Áńtíókù. 6 Wọ́n mú wọn wá sọ́dọ̀ àwọn àpọ́sítélì, lẹ́yìn tí àwọn àpọ́sítélì gbàdúrà, wọ́n gbé ọwọ́ lé wọn.+

7 Nítorí náà, ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ń gbilẹ̀ nìṣó,+ iye àwọn ọmọ ẹ̀yìn sì ń pọ̀ sí i gidigidi+ ní Jerúsálẹ́mù; ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn àlùfáà sì bẹ̀rẹ̀ sí í tẹ́wọ́ gba* ìgbàgbọ́ náà.+

8 Nígbà náà, Sítéfánù, tó kún fún oore Ọlọ́run àti agbára, ń ṣe àwọn ohun ìyanu* ńlá àti àwọn iṣẹ́ àmì láàárín àwọn èèyàn. 9 Àmọ́ àwọn ọkùnrin kan látinú àwùjọ tí wọ́n ń pè ní Sínágọ́gù Àwọn Olómìnira wá, pẹ̀lú àwọn ará Kírénè àti àwọn ará Alẹkisáńdíríà àti lára àwọn tó wá láti Sìlíṣíà àti Éṣíà, wọ́n wá bá Sítéfánù fa ọ̀rọ̀. 10 Àmọ́ wọn ò lè dúró níwájú rẹ̀ nítorí ọgbọ́n àti ẹ̀mí tó fi ń sọ̀rọ̀.+ 11 Lẹ́yìn náà, wọ́n sún àwọn kan ní bòókẹ́lẹ́ pé kí wọ́n sọ pé: “A gbọ́ tó ń sọ ọ̀rọ̀ òdì sí Mósè àti Ọlọ́run.” 12 Wọ́n ru àwọn èèyàn àti àwọn àgbààgbà pẹ̀lú àwọn akọ̀wé òfin sókè, wọ́n wá bá a lójijì, wọ́n fipá gbá a mú, wọ́n sì mú un lọ sí Sàhẹ́ndìrìn. 13 Wọ́n mú àwọn ẹlẹ́rìí èké wá, tí wọ́n sọ pé: “Ọkùnrin yìí kò jáwọ́ nínú sísọ ọ̀rọ̀ òdì sí ibi mímọ́ yìí àti sí Òfin. 14 Bí àpẹẹrẹ, a gbọ́ tó sọ pé Jésù ará Násárẹ́tì máa wó ibí yìí palẹ̀, á sì yí àwọn àṣà tí Mósè fi lé wa lọ́wọ́ pa dà.”

15 Bí gbogbo àwọn tó jókòó ní Sàhẹ́ndìrìn ṣe tẹjú mọ́ ọn, wọ́n rí i pé ojú rẹ̀ dà bí ojú áńgẹ́lì.

7 Àmọ́ àlùfáà àgbà béèrè lọ́wọ́ Sítéfánù pé: “Ṣé bẹ́ẹ̀ ni ọ̀rọ̀ náà rí?” 2 Sítéfánù dáhùn pé: “Ẹ̀yin èèyàn, ẹ̀yin ará àti ẹ̀yin bàbá, ẹ fetí sílẹ̀. Ọlọ́run ògo fara han Ábúráhámù baba ńlá wa nígbà tó wà ní Mesopotámíà, kí ó tó máa gbé ní Háránì,+ 3 ó sì sọ fún un pé: ‘Jáde kúrò ní ilẹ̀ rẹ àti kúrò lọ́dọ̀ àwọn mọ̀lẹ́bí rẹ, kí o sì wá sí ilẹ̀ tí màá fi hàn ọ́.’+ 4 Lẹ́yìn náà, ó jáde kúrò ní ilẹ̀ àwọn ará Kálídíà, ó sì ń gbé ní Háránì. Lẹ́yìn tí bàbá rẹ̀ kú,+ Ọlọ́run darí rẹ̀ láti ibẹ̀ pé kí ó lọ máa gbé ní ilẹ̀ tí ẹ̀ ń gbé báyìí.+ 5 Síbẹ̀, kò fún un ní ogún kankan nínú rẹ̀, rárá, kò tiẹ̀ fún un ní ibi tó lè gbẹ́sẹ̀ lé; àmọ́ ó ṣèlérí pé òun máa fún un láti fi ṣe ohun ìní, lẹ́yìn rẹ̀ òun á fún ọmọ* rẹ̀,+ bó tiẹ̀ jẹ́ pé kò tíì ní ọmọ kankan. 6 Yàtọ̀ síyẹn, Ọlọ́run sọ fún un pé àwọn ọmọ* rẹ̀ máa di àjèjì ní ilẹ̀ tí kì í ṣe tiwọn, àwọn èèyàn ibẹ̀ á fi wọ́n ṣe ẹrú, wọ́n á sì fìyà jẹ wọ́n* fún ọgọ́rùn-ún mẹ́rin (400) ọdún.+ 7 ‘Màá dá orílẹ̀-èdè tí wọ́n máa ṣẹrú fún lẹ́jọ́,’+ ni Ọlọ́run wí, ‘lẹ́yìn nǹkan wọ̀nyí, wọ́n á jáde, wọ́n á sì ṣe iṣẹ́ ìsìn mímọ́ fún mi ní ibí yìí.’+

8 “Ó tún fún Ábúráhámù ní májẹ̀mú ìdádọ̀dọ́,*+ ó sì bí Ísákì,+ ó dádọ̀dọ́ rẹ̀* ní ọjọ́ kẹjọ,+ Ísákì sì bí* Jékọ́bù, Jékọ́bù sì bí àwọn olórí ìdílé* méjìlá (12). 9 Àwọn olórí ìdílé náà jowú Jósẹ́fù,+ wọ́n sì tà á sí Íjíbítì.+ Àmọ́ Ọlọ́run wà pẹ̀lú rẹ̀,+ 10 ó gbà á nínú gbogbo ìpọ́njú rẹ̀, ó ṣe ojúure sí i, ó sì fún un ní ọgbọ́n níwájú Fáráò ọba Íjíbítì. Ó yàn án láti ṣàkóso Íjíbítì àti gbogbo ilé rẹ̀.+ 11 Àmọ́ ìyàn kan mú ní gbogbo Íjíbítì àti Kénáánì, ìpọ́njú ńlá ni, àwọn baba ńlá wa ò sì rí nǹkan kan jẹ.+ 12 Àmọ́ Jékọ́bù gbọ́ pé oúnjẹ* wà ní Íjíbítì, ó sì rán àwọn baba ńlá wa jáde ní ìgbà àkọ́kọ́.+ 13 Nígbà kejì, Jósẹ́fù jẹ́ kí àwọn arákùnrin rẹ̀ mọ òun, Fáráò náà sì mọ ìdílé Jósẹ́fù.+ 14 Torí náà, Jósẹ́fù ránṣẹ́ pe Jékọ́bù bàbá rẹ̀ àti gbogbo mọ̀lẹ́bí rẹ̀ láti ibẹ̀,+ gbogbo wọn* lápapọ̀ jẹ́ márùndínlọ́gọ́rin (75).+ 15 Jékọ́bù lọ sí Íjíbítì,+ ó sì kú síbẹ̀,+ ohun kan náà ló ṣẹlẹ̀ sí àwọn baba ńlá wa.+ 16 Wọ́n gbé wọn lọ sí Ṣékémù, wọ́n sì tẹ́ wọn sínú ibojì tí Ábúráhámù fi owó fàdákà rà lọ́wọ́ àwọn ọmọ Hámórì ní Ṣékémù.+

17 “Bó ṣe ku díẹ̀ kí ìlérí tí Ọlọ́run ṣe fún Ábúráhámù ṣẹ, àwọn èèyàn náà gbilẹ̀, wọ́n sì di púpọ̀ ní Íjíbítì, 18 títí ọba míì fi jẹ ní Íjíbítì, ẹni tí kò mọ Jósẹ́fù.+ 19 Ẹni yìí lo ọgbọ́n àrékérekè fún àwọn èèyàn wa, ó sì fipá mú àwọn bàbá láti pa àwọn ọmọ wọn jòjòló tì, kí wọ́n má bàa wà láàyè.+ 20 Lákòókò yẹn, wọ́n bí Mósè, Ọlọ́run sì fún un lẹ́wà gan-an.* Wọ́n fi oṣù mẹ́ta tọ́jú rẹ̀* ní ilé bàbá rẹ̀.+ 21 Àmọ́ nígbà tí wọ́n pa á tì,*+ ọmọbìnrin Fáráò gbé e, ó sì tọ́ ọ dàgbà bí ọmọ òun fúnra rẹ̀.+ 22 Nítorí náà, wọ́n kọ́ Mósè ní gbogbo ọgbọ́n àwọn ará Íjíbítì. Kódà, ó di alágbára ní ọ̀rọ̀ àti ní ìṣe.+

23 “Nígbà tó pé ẹni ogójì (40) ọdún, ó wá sí i lọ́kàn* láti lọ wo* àwọn arákùnrin rẹ̀, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.+ 24 Nígbà tó tajú kán rí ọ̀kan lára wọn tí ará Íjíbítì kan ń hùwà àìdáa sí, ó gbèjà rẹ̀, ó sì bá ẹni tí wọ́n ń ṣàìdáa sí náà gbẹ̀san, ó pa ará Íjíbítì náà. 25 Ó rò pé àwọn arákùnrin òun máa lóye pé Ọlọ́run máa ti ọwọ́ òun gbà wọ́n là, àmọ́ kò yé wọn. 26 Lọ́jọ́ kejì, ó yọ sí wọn nígbà tí wọ́n ń jà, ó sì fẹ́ bá wọn parí ìjà ní àlàáfíà, ó sọ pé: ‘Ẹ̀yin èèyàn, arákùnrin ni yín. Kí ló dé tí ẹ̀ ń hùwà àìdáa sí ara yín?’ 27 Àmọ́ ẹni tó ń fìyà jẹ ọmọnìkejì rẹ̀ tì í dà nù, ó ní: ‘Ta ló fi ọ́ ṣe alákòóso àti onídàájọ́ lé wa lórí? 28 Àbí o tún fẹ́ pa mí bí o ṣe pa ará Íjíbítì yẹn lánàá?’ 29 Bí Mósè ṣe gbọ́ ọ̀rọ̀ yìí, ó fẹsẹ̀ fẹ, ó sì lọ di àjèjì ní ilẹ̀ Mídíánì, ibẹ̀ ló ti bí ọmọkùnrin méjì.+

30 “Lẹ́yìn ogójì (40) ọdún, áńgẹ́lì kan fara hàn án ní aginjù Òkè Sínáì nínú ọwọ́ iná tó ń jó lára igi ẹlẹ́gùn-ún.+ 31 Nígbà tí Mósè rí i, ohun tó rí yà á lẹ́nu. Àmọ́ bí ó ṣe ń sún mọ́ ọn láti wádìí ohun tí ó jẹ́, ó gbọ́ ohùn Jèhófà* pé: 32 ‘Èmi ni Ọlọ́run àwọn baba ńlá rẹ, Ọlọ́run Ábúráhámù àti ti Ísákì àti ti Jékọ́bù.’+ Mósè bẹ̀rẹ̀ sí í gbọ̀n, kò sì gbójúgbóyà láti sọ pé òun fẹ́ wádìí sí i. 33 Jèhófà* sọ fún un pé: ‘Bọ́ bàtà ẹsẹ̀ rẹ, torí ilẹ̀ mímọ́ ni ibi tí o dúró sí. 34 Mo ti rí bí wọ́n ṣe ń fìyà jẹ àwọn èèyàn mi tó wà ní Íjíbítì, mo sì ti gbọ́ bí wọ́n ṣe ń kérora,+ mo ti sọ̀ kalẹ̀ wá láti gbà wọ́n sílẹ̀. Ní báyìí, wá, màá rán ọ lọ sí Íjíbítì.’ 35 Mósè yìí kan náà, tí wọ́n sọ pé àwọn ò mọ̀ rí, tí wọ́n sọ fún pé: ‘Ta ló fi ọ́ ṣe alákòóso àti onídàájọ́?’+ òun kan náà ni Ọlọ́run rán+ láti jẹ́ alákòóso àti olùdáǹdè nípasẹ̀ áńgẹ́lì tó fara hàn án látinú igi ẹlẹ́gùn-ún. 36 Ọkùnrin yìí mú wọn jáde,+ ó ṣe àwọn ohun ìyanu* àti iṣẹ́ àmì ní Íjíbítì+ àti ní Òkun Pupa+ àti ní aginjù fún ogójì (40) ọdún.+

37 “Mósè yìí ló sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé: ‘Ọlọ́run máa gbé wòlíì kan bí èmi dìde fún yín láàárín àwọn arákùnrin yín.’+ 38 Ẹni yìí wà lára ìjọ tó wà ní aginjù, ó wà pẹ̀lú áńgẹ́lì+ tó bá a sọ̀rọ̀+ lórí Òkè Sínáì pẹ̀lú àwọn baba ńlá wa, ó sì gba àwọn ọ̀rọ̀ ìkéde mímọ́ tó jẹ́ ààyè láti fún wa.+ 39 Àmọ́ àwọn baba ńlá wa kọ̀, wọn ò ṣègbọràn sí i, ṣe ni wọ́n tì í sẹ́gbẹ̀ẹ́ kan,+ wọ́n sì pa dà sí Íjíbítì nínú ọkàn wọn,+ 40 wọ́n sọ fún Áárónì pé: ‘Ṣe àwọn ọlọ́run fún wa tó máa ṣáájú wa. Torí a ò mọ ohun tó ti ṣẹlẹ̀ sí Mósè yìí, ẹni tó kó wa kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì.’+ 41 Nítorí náà, wọ́n ṣe ère ọmọ màlúù kan lákòókò yẹn, wọ́n mú ẹbọ wá fún ère náà, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í gbádùn ara wọn nítorí àwọn iṣẹ́ ọwọ́ wọn.+ 42 Torí náà, Ọlọ́run pa dà lẹ́yìn wọn, ó sì fi wọ́n sílẹ̀ kí wọ́n lọ máa sin àwọn ọmọ ogun ọ̀run,+ bó ṣe wà lákọsílẹ̀ nínú ìwé àwọn Wòlíì pé: ‘Èmi kọ́ ni ẹ̀ ń mú ọrẹ àti ẹbọ wá fún ní gbogbo ogójì (40) ọdún tí ẹ fi wà ní aginjù, àbí èmi ni, ilé Ísírẹ́lì? 43 Àmọ́ àgọ́ Mólókù+ àti ìràwọ̀ ọlọ́run Réfánì tí ẹ̀ ń gbé ga ni, àwọn ère tí ẹ ṣe láti máa jọ́sìn wọn. Nítorí náà, màá lé yín dà nù kọjá Bábílónì.’+

44 “Àwọn baba ńlá wa ní àgọ́ ẹ̀rí nínú aginjù, bí Ọlọ́run ṣe pa á láṣẹ nígbà tó sọ fún Mósè pé kó ṣe é bí èyí tí ó rí.+ 45 Àwọn baba ńlá wa jogún rẹ̀, wọ́n sì gbé e wá nígbà tí wọ́n ń tẹ̀ lé Jóṣúà bọ̀ ní ilẹ̀ àwọn orílẹ̀-èdè,+ àwọn tí Ọlọ́run lé jáde kúrò níwájú àwọn baba ńlá wa.+ Ó sì wà níbẹ̀ títí di ìgbà ayé Dáfídì. 46 Ó rí ojú rere Ọlọ́run, ó sì ní kó fún òun láǹfààní láti kọ́ ibùgbé fún Ọlọ́run Jékọ́bù.+ 47 Àmọ́ Sólómọ́nì ló kọ́ ilé fún un.+ 48 Síbẹ̀, Ẹni Gíga Jù Lọ kì í gbé àwọn ilé tí a fi ọwọ́ kọ́,+ bí wòlíì kan ṣe sọ pé: 49 ‘Ọ̀run ni ìtẹ́ mi,+ ayé sì ni àpótí ìtìsẹ̀ mi.+ Irú ilé wo lẹ fẹ́ kọ́ fún mi? ni Jèhófà* wí. Àbí ibo ni ibi ìsinmi mi? 50 Ọwọ́ mi ni ó ṣe gbogbo nǹkan yìí, àbí òun kọ́?’+

51 “Ẹ̀yin olóríkunkun àti aláìkọlà* ọkàn àti etí, gbogbo ìgbà lẹ̀ ń ta ko ẹ̀mí mímọ́; bí àwọn baba ńlá yín ti ṣe náà lẹ̀ ń ṣe.+ 52 Èwo nínú àwọn wòlíì ni àwọn baba ńlá yín kò ṣe inúnibíni sí?+ Bẹ́ẹ̀ ni, wọ́n pa àwọn tó kéde pé olódodo náà ń bọ̀,+ ẹni tí ẹ dalẹ̀ rẹ̀ tí ẹ sì pa,+ 53 ẹ̀yin tí ẹ gba Òfin bí ó ṣe wá látọ̀dọ̀ àwọn áńgẹ́lì+ àmọ́ tí ẹ kò pa á mọ́.”

54 Tóò, nígbà tí wọ́n gbọ́ àwọn nǹkan yìí, wọ́n gbaná jẹ,* wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í wa eyín wọn pọ̀ sí i. 55 Àmọ́ òun, tó ti kún fún ẹ̀mí mímọ́, ń wo ọ̀run, ó sì tajú kán rí ògo Ọlọ́run àti ti Jésù tó dúró ní ọwọ́ ọ̀tún Ọlọ́run,+ 56 ó sọ pé: “Ẹ wò ó! Mo rí i tí ọ̀run ṣí sílẹ̀, Ọmọ èèyàn+ sì dúró ní ọwọ́ ọ̀tún Ọlọ́run.”+ 57 Ni wọ́n bá figbe ta bí ohùn wọn ṣe lè ròkè tó, wọ́n fi ọwọ́ bo etí wọn, gbogbo wọn sì ṣùrù bò ó. 58 Lẹ́yìn tí wọ́n jù ú sẹ́yìn òde ìlú, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í sọ ọ́ lókùúta.+ Àwọn ẹlẹ́rìí+ kó aṣọ àwọ̀lékè wọn síbi ẹsẹ̀ ọ̀dọ́kùnrin kan tí wọ́n ń pè ní Sọ́ọ̀lù.+ 59 Bí wọ́n ṣe ń sọ òkúta lu Sítéfánù, ó bẹ̀bẹ̀ pé: “Jésù Olúwa, gba ẹ̀mí mi.” 60 Lẹ́yìn náà, ó kúnlẹ̀, ó sì fi ohùn líle ké jáde pé: “Jèhófà,* má ka ẹ̀ṣẹ̀ yìí sí wọn lọ́rùn.”+ Lẹ́yìn tó sọ èyí, ó sùn nínú ikú.

8 Sọ́ọ̀lù, ní tirẹ̀, fọwọ́ sí bí wọ́n ṣe pa Sítéfánù.+

Ní ọjọ́ yẹn, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe inúnibíni tó lágbára sí ìjọ tó wà ní Jerúsálẹ́mù; gbogbo àwọn ọmọ ẹ̀yìn tú ká lọ sí gbogbo agbègbè Jùdíà àti Samáríà, àwọn àpọ́sítélì nìkan ni kò tú ká.+ 2 Àmọ́ àwọn ọkùnrin olùfọkànsìn gbé Sítéfánù lọ sin, wọ́n sì ṣọ̀fọ̀ gan-an nítorí rẹ̀. 3 Ṣùgbọ́n Sọ́ọ̀lù bẹ̀rẹ̀ sí í hùwà ìkà sí ìjọ. Bó ṣe ń jáde nínú ilé kan ló ń wọ òmíì, ó ń wọ́ tọkùnrin tobìnrin jáde, ó sì ń jù wọ́n sẹ́wọ̀n.+

4 Síbẹ̀, àwọn tó ti tú ká ń lọ káàkiri ilẹ̀ náà, wọ́n ń kéde ìhìn rere ọ̀rọ̀ náà.+ 5 Lásìkò yìí, Fílípì lọ sí ìlú* Samáríà,+ ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í wàásù nípa Kristi fún wọn. 6 Ọ̀pọ̀ èèyàn pọkàn pọ̀ sórí ohun tí Fílípì ń sọ, wọ́n ń fetí sílẹ̀, wọ́n sì ń wo àwọn iṣẹ́ àmì tó ń ṣe. 7 Nítorí ọ̀pọ̀ ló ní àwọn ẹ̀mí àìmọ́, àwọn ẹ̀mí yìí á kígbe ní ohùn rara, wọ́n á sì jáde.+ Yàtọ̀ síyẹn, ọ̀pọ̀ àwọn tó ní àrùn rọpárọsẹ̀ àti àwọn tó yarọ rí ìwòsàn. 8 Nítorí náà, ìdùnnú ṣubú layọ̀ ní ìlú yẹn.

9 Lákòókò yẹn, ọkùnrin kan wà tó ń jẹ́ Símónì ní ìlú náà, ṣáájú àkókò yìí, ó ti ń ṣe iṣẹ́ idán pípa, ó ń mú kí ẹnu ya orílẹ̀-èdè Samáríà, ó sì ń sọ pé ẹni ńlá ni òun. 10 Gbogbo wọn, látorí ẹni tó kéré jù lọ dórí ẹni tó tóbi jù lọ, ló ń fiyè sí i, tí wọ́n sì ń sọ pé: “Ọkùnrin yìí ni Agbára Ọlọ́run, tí à ń pè ní Títóbi.” 11 Nítorí náà, wọ́n á fiyè sí i torí pé ó ti pẹ́ díẹ̀ tó ti ń fi iṣẹ́ idán rẹ̀ mú kí ẹnu yà wọ́n. 12 Àmọ́ nígbà tí wọ́n gba Fílípì gbọ́, ẹni tó ń kéde ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run+ àti orúkọ Jésù Kristi, tọkùnrin tobìnrin wọn sì ń ṣèrìbọmi.+ 13 Símónì náà di onígbàgbọ́, lẹ́yìn tó ṣèrìbọmi, ó wà pẹ̀lú Fílípì;+ ó sì ń yà á lẹ́nu bó ṣe ń rí àwọn iṣẹ́ àmì àti àwọn iṣẹ́ agbára ńlá tó ń ṣẹlẹ̀.

14 Nígbà tí àwọn àpọ́sítélì tó wà ní Jerúsálẹ́mù gbọ́ pé Samáríà ti gba ọ̀rọ̀ Ọlọ́run,+ wọ́n rán Pétérù àti Jòhánù sí wọn; 15 àwọn yìí wá, wọ́n sì gbàdúrà fún wọn kí wọ́n lè gba ẹ̀mí mímọ́.+ 16 Nítorí kò tíì bà lé ẹnikẹ́ni nínú wọn, a kàn ṣì batisí wọn ní orúkọ Jésù Olúwa ni.+ 17 Nígbà náà, wọ́n gbé ọwọ́ lé wọn,+ wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í rí ẹ̀mí mímọ́ gbà.

18 Nígbà tí Símónì rí i pé àwọn èèyàn ń rí ẹ̀mí gbà tí àwọn àpọ́sítélì bá ti gbọ́wọ́ lé wọn, ó fi owó lọ̀ wọ́n, 19 ó sọ pé: “Ẹ fún èmi náà ní àṣẹ yìí, kí ẹnikẹ́ni tí mo bá gbé ọwọ́ mi lé lè rí ẹ̀mí mímọ́ gbà.” 20 Àmọ́ Pétérù sọ fún un pé: “Kí fàdákà rẹ ṣègbé pẹ̀lú rẹ, torí o rò pé o lè fi owó ra ẹ̀bùn ọ̀fẹ́ Ọlọ́run.+ 21 O kò ní ipa tàbí ìpín kankan nínú ọ̀rọ̀ yìí, nítorí pé ọkàn rẹ kò tọ́ lójú Ọlọ́run. 22 Torí náà, ronú pìwà dà ìwà búburú rẹ yìí, kí o sì rawọ́ ẹ̀bẹ̀ sí Jèhófà* pé, tó bá ṣeé ṣe, kí ó dárí èrò ibi tó wà lọ́kàn rẹ jì ọ́; 23 torí mo rí i pé májèlé kíkorò* àti ẹrú àìṣòdodo ni ọ́.” 24 Ni Símónì bá dá wọn lóhùn pé: “Ẹ bá mi rawọ́ ẹ̀bẹ̀ sí Jèhófà* kí ìkankan nínú ohun tí ẹ sọ má bàa ṣẹlẹ̀ sí mi.”

25 Nítorí náà, nígbà tí wọ́n ti jẹ́rìí kúnnákúnná, tí wọ́n sì ti sọ ọ̀rọ̀ Jèhófà,* wọ́n bẹ̀rẹ̀ ìrìn wọn pa dà sí Jerúsálẹ́mù, wọ́n sì ń kéde ìhìn rere ní ọ̀pọ̀ abúlé àwọn ará Samáríà.+

26 Àmọ́, áńgẹ́lì Jèhófà*+ bá Fílípì sọ̀rọ̀, ó ní: “Dìde kí o sì lọ sí gúúsù ní ọ̀nà tó lọ láti Jerúsálẹ́mù sí Gásà.” (Èyí jẹ́ ọ̀nà aṣálẹ̀.) 27 Ló bá dìde, ó lọ, sì wò ó! ìwẹ̀fà* ará Etiópíà kan, ọkùnrin tó wà nípò àṣẹ lábẹ́ Káńdésì ọbabìnrin àwọn ará Etiópíà, òun ló ń bójú tó gbogbo ìṣúra rẹ̀. Ó lọ jọ́sìn ní Jerúsálẹ́mù,+ 28 ó sì ń pa dà bọ̀, ó jókòó sínú kẹ̀kẹ́ ẹṣin rẹ̀, ó sì ń ka ìwé wòlíì Àìsáyà sókè. 29 Nítorí náà, ẹ̀mí sọ fún Fílípì pé: “Lọ, kí o sì sún mọ́ kẹ̀kẹ́ ẹṣin yìí.” 30 Fílípì sáré lọ sí ẹ̀gbẹ́ rẹ̀, ó sì gbọ́ tí ó ń ka ìwé wòlíì Àìsáyà sókè, ó wá bi í pé: “Ǹjẹ́ o tiẹ̀ lóye* ohun tí ò ń kà?” 31 Ó dáhùn pé: “Báwo ni mo ṣe lè lóye, láìjẹ́ pé ẹnì kan tọ́ mi sọ́nà?” Torí náà, ó rọ Fílípì pé kó gòkè, kó sì jókòó pẹ̀lú òun. 32 Àyọkà Ìwé Mímọ́ tó ń kà nìyí: “Wọ́n mú un wá bí àgùntàn sí ibi tí wọ́n ti fẹ́ pa á, bí ọ̀dọ́ àgùntàn tó dákẹ́ níwájú àwọn tó ń rẹ́ irun rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni kò la ẹnu rẹ̀.+ 33 Nígbà tí wọ́n ń pẹ̀gàn rẹ̀, wọn ò ṣe ìdájọ́ òdodo fún un.+ Ta ló máa sọ kúlẹ̀kúlẹ̀ ìran rẹ̀? Nítorí wọ́n gba ẹ̀mí rẹ̀ kúrò ní ayé.”+

34 Ìwẹ̀fà náà wá béèrè lọ́wọ́ Fílípì pé: “Mo bẹ̀ ọ́, ta ni wòlíì náà ń sọ nípa rẹ̀? Ṣé nípa ara rẹ̀ ni àbí ẹlòmíì?” 35 Ni Fílípì bá tẹnu bọ̀rọ̀, ó bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú Ìwé Mímọ́ yìí, ó sì kéde ìhìn rere nípa Jésù fún un. 36 Bí wọ́n ṣe ń lọ lójú ọ̀nà, wọ́n dé ibi tí omi wà, ìwẹ̀fà náà sì sọ pé: “Wò ó! Omi rèé; kí ló ń dá mi dúró láti ṣèrìbọmi?” 37* —— 38 Ló bá pàṣẹ pé kí kẹ̀kẹ́ ẹṣin náà dúró, Fílípì àti ìwẹ̀fà náà wá wọ inú omi, Fílípì sì ṣèrìbọmi fún un. 39 Nígbà tí wọ́n jáde nínú omi, ní kíá, ẹ̀mí Jèhófà* darí Fílípì lọ, ìwẹ̀fà náà kò sì rí i mọ́, àmọ́ ó bá ọ̀nà rẹ̀ lọ, inú rẹ̀ sì ń dùn. 40 Ní ti Fílípì, ó bá ara rẹ̀ ní Áṣídódù, ó gba ìpínlẹ̀ náà kọjá, ó sì ń kéde ìhìn rere fún gbogbo àwọn ìlú títí ó fi dé Kesaríà.+

9 Àmọ́ Sọ́ọ̀lù, tí inú rẹ̀ ṣì ń ru, tó sì ń fikú halẹ̀ mọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn Olúwa,+ lọ bá àlùfáà àgbà, 2 ó sì ní kí ó fún òun ní àwọn lẹ́tà sí àwọn sínágọ́gù ní Damásíkù, kí ó lè mú ẹnikẹ́ni tó bá rí tí ó jẹ́ ti Ọ̀nà Náà+ wá sí Jerúsálẹ́mù ní dídè, àti ọkùnrin àti obìnrin.

3 Bí ó ṣe ń rin ìrìn àjò lọ, tó sì ń sún mọ́ Damásíkù, lójijì, ìmọ́lẹ̀ kan láti ọ̀run kọ mànà yí i ká,+ 4 ó ṣubú lulẹ̀, ó sì gbọ́ tí ohùn kan sọ fún un pé: “Sọ́ọ̀lù, Sọ́ọ̀lù, kí nìdí tí o fi ń ṣe inúnibíni sí mi?” 5 Ó béèrè pé: “Ta ni ọ́, Olúwa?” Ó sọ pé: “Èmi ni Jésù,+ ẹni tí ò ń ṣe inúnibíni sí.+ 6 Ní báyìí, dìde, kí o sì wọnú ìlú, wọ́n á sọ ohun tí o máa ṣe fún ọ.” 7 Àwọn ọkùnrin tí wọ́n jọ ń rin ìrìn àjò dúró, wọn ò lè sọ̀rọ̀, ní tòótọ́, wọ́n ń gbọ́ ìró, àmọ́ wọn ò rí ẹnì kankan.+ 8 Sọ́ọ̀lù wá dìde nílẹ̀, bó tiẹ̀ jẹ́ pé ojú rẹ̀ là sílẹ̀, kò rí nǹkan kan. Torí náà, wọ́n dì í lọ́wọ́ mú, wọ́n sì mú un wọ Damásíkù. 9 Ọjọ́ mẹ́ta ni kò fi rí nǹkan kan,+ kò jẹ, bẹ́ẹ̀ ni kò mu.

10 Ọmọ ẹ̀yìn kan wà ní Damásíkù tó ń jẹ́ Ananáyà,+ Olúwa sọ fún un nínú ìran pé: “Ananáyà!” Ó sọ pé: “Èmi nìyí, Olúwa.” 11 Olúwa sọ fún un pé: “Dìde, lọ sí ojú ọ̀nà tí wọ́n ń pè ní Títọ́, kí o sì wá ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Sọ́ọ̀lù láti Tásù+ ní ilé Júdásì. Wò ó! ó ń gbàdúrà, 12 àti pé nínú ìran, ó ti rí ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Ananáyà tí ó wọlé wá, tí ó sì gbé ọwọ́ lé e kí ó lè tún máa ríran.”+ 13 Àmọ́ Ananáyà dáhùn pé: “Olúwa, mo ti gbọ́ nípa ọkùnrin yìí lẹ́nu ọ̀pọ̀ èèyàn, mo ti gbọ́ gbogbo jàǹbá tó ṣe sí àwọn ẹni mímọ́ rẹ ní Jerúsálẹ́mù. 14 Ní báyìí, ó ti gba àṣẹ lọ́wọ́ àwọn olórí àlùfáà láti mú* gbogbo àwọn tó ń ké pe orúkọ rẹ.”+ 15 Àmọ́ Olúwa sọ fún un pé: “Lọ! nítorí ohun èlò tí a ti yàn ni ọkùnrin yìí jẹ́ fún mi+ láti mú orúkọ mi lọ sọ́dọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè+ àti àwọn ọba+ àti àwọn ọmọ Ísírẹ́lì. 16 Nítorí màá fi hàn án ní kedere bí ìyà tó máa jẹ nítorí orúkọ mi ṣe máa pọ̀ tó.”+

17 Nítorí náà, Ananáyà lọ, ó sì wọ ilé náà, ó gbé ọwọ́ lé e, ó sì sọ pé: “Sọ́ọ̀lù, arákùnrin, Jésù Olúwa tó fara hàn ọ́ lójú ọ̀nà tí ò ń gbà bọ̀ ló rán mi kí o lè tún máa ríran, kí o sì kún fún ẹ̀mí mímọ́.”+ 18 Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, ohun tó rí bí ìpẹ́ já bọ́ láti ojú rẹ̀, ó sì tún ríran. Lẹ́yìn náà, ó dìde, ó sì ṣèrìbọmi, 19 ó jẹun, ó sì lókun.

Ó lo ọjọ́ mélòó kan pẹ̀lú àwọn ọmọ ẹ̀yìn ní Damásíkù,+ 20 lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, ó bẹ̀rẹ̀ sí í wàásù nípa Jésù nínú àwọn sínágọ́gù, pé ẹni yìí ni Ọmọ Ọlọ́run. 21 Àmọ́ ẹnu ya gbogbo àwọn tó ń gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀, wọ́n sì ń sọ pé: “Ọkùnrin yìí kọ́ ló ń kó àwọn tó wà ní Jerúsálẹ́mù, tí wọ́n ń ké pe orúkọ yìí ni?+ Ṣé kì í ṣe torí kó lè fàṣẹ mú wọn, kó sì mú wọn* lọ sọ́dọ̀ àwọn olórí àlùfáà ló ṣe wá síbí ni?”+ 22 Àmọ́ Sọ́ọ̀lù ń gba agbára kún agbára, ó sì ń pa àwọn Júù tó ń gbé ní Damásíkù lẹ́nu mọ́, bí ó ṣe ń fi ẹ̀rí tó bọ́gbọ́n mu hàn pé Jésù ni Kristi náà.+

23 Lẹ́yìn ọ̀pọ̀ ọjọ́, àwọn Júù gbìmọ̀ pọ̀ láti pa á.+ 24 Àmọ́, Sọ́ọ̀lù gbọ́ nípa ohun tí wọ́n ń gbèrò sí òun. Kódà, tọ̀sántòru ni wọ́n ń ṣọ́ àwọn ẹnubodè lójú méjèèjì, kí wọ́n lè pa á. 25 Torí náà, àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ gbé e, wọ́n sì sọ̀ ọ́ kalẹ̀ gba ojú ihò kan lára ògiri lóru, wọ́n sọ̀ ọ́ kalẹ̀ nínú apẹ̀rẹ̀.+

26 Nígbà tó dé Jerúsálẹ́mù,+ ó sapá láti dara pọ̀ mọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn, àmọ́ gbogbo wọn ń bẹ̀rù rẹ̀, torí wọn ò gbà gbọ́ pé ọmọ ẹ̀yìn ni. 27 Nítorí náà, Bánábà+ ràn án lọ́wọ́, ó mú un lọ bá àwọn àpọ́sítélì, ó sì sọ kúlẹ̀kúlẹ̀ bí ó ṣe rí Olúwa ní ojú ọ̀nà+ fún wọn àti pé Olúwa bá a sọ̀rọ̀. Ó tún sọ bó ṣe fìgboyà sọ̀rọ̀ nípa orúkọ Jésù ní Damásíkù.+ 28 Nítorí náà, ó dúró tì wọ́n, ó sì ń rìn fàlàlà* ní Jerúsálẹ́mù, ó ń fìgboyà sọ̀rọ̀ nípa orúkọ Olúwa. 29 Ó ń sọ̀rọ̀, ó sì ń bá àwọn Júù tó ń sọ èdè Gíríìkì fa ọ̀rọ̀, àmọ́ àwọn yìí gbìyànjú láti pa á.+ 30 Nígbà tí àwọn ará gbọ́ nípa èyí, wọ́n mú un wá sí Kesaríà, wọ́n sì rán an lọ sí Tásù.+

31 Ní tòótọ́, nígbà náà, ìjọ tó wà jákèjádò Jùdíà àti Gálílì àti Samáríà+ wọnú àkókò àlàáfíà, à ń gbé e ró; ó ń gbèrú sí i bó ṣe ń rìn nínú ìbẹ̀rù Jèhófà* àti nínú ìtùnú ẹ̀mí mímọ́.+

32 Bí Pétérù ṣe ń rìnrìn àjò gba gbogbo agbègbè yẹn kọjá, ó wá sọ́dọ̀ àwọn ẹni mímọ́ tó ń gbé ní Lídà.+ 33 Ó rí ọkùnrin kan níbẹ̀ tó ń jẹ́ Énéà, ọdún mẹ́jọ ló ti wà ní ìdùbúlẹ̀ lórí ibùsùn rẹ̀, torí pé ó ní àrùn rọpárọsẹ̀. 34 Pétérù sọ fún un pé: “Énéà, Jésù Kristi mú ọ lára dá.+ Dìde, kí o sì tẹ́ ibùsùn rẹ.”+ Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, ó dìde. 35 Nígbà tí gbogbo àwọn tó ń gbé ní Lídà àti Pẹ̀tẹ́lẹ̀ Ṣárónì rí i, wọ́n yíjú sọ́dọ̀ Olúwa.

36 Ọmọ ẹ̀yìn kan wà ní Jópà tó ń jẹ́ Tàbítà, èyí tó túmọ̀ sí “Dọ́káàsì,”* tí a bá túmọ̀ rẹ̀. Àwọn iṣẹ́ rere àti ọrẹ àánú tó ń fúnni pọ̀ gidigidi. 37 Àmọ́ lákòókò yẹn, ó ṣàìsàn, ó sì kú. Torí náà, wọ́n wẹ̀ ẹ́, wọ́n sì tẹ́ ẹ sí yàrá òkè. 38 Nígbà tí àwọn ọmọ ẹ̀yìn gbọ́ pé Pétérù wà ní Lídà, torí pé Lídà ò jìnnà sí Jópà, wọ́n rán ọkùnrin méjì lọ bá a láti pàrọwà fún un pé: “Jọ̀wọ́ tètè máa bọ̀ lọ́dọ̀ wa.” 39 Ni Pétérù bá dìde, ó sì bá wọn lọ. Nígbà tó débẹ̀, wọ́n mú un lọ sí yàrá òkè; gbogbo àwọn opó sì wá sọ́dọ̀ rẹ̀, wọ́n ń sunkún, wọ́n sì ń fi ọ̀pọ̀ aṣọ àti ẹ̀wù* tí Dọ́káàsì ti ṣe nígbà tó wà lọ́dọ̀ wọn hàn án. 40 Pétérù wá ní kí gbogbo èèyàn bọ́ síta,+ ó kúnlẹ̀, ó sì gbàdúrà. Lẹ́yìn náà, ó yíjú sí òkú náà, ó sọ pé: “Tàbítà, dìde!” Obìnrin náà lajú, bó ṣe tajú kán rí Pétérù, ó dìde jókòó.+ 41 Pétérù na ọwọ́ sí i, ó gbé e dìde, ó sì pe àwọn ẹni mímọ́ àti àwọn opó, ó wá fà á lé wọn lọ́wọ́ láàyè.+ 42 Ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí tàn káàkiri Jópà, ọ̀pọ̀ èèyàn sì di onígbàgbọ́ nínú Olúwa.+ 43 Ó lo ọjọ́ mélòó kan sí i ní Jópà lọ́dọ̀ oníṣẹ́ awọ kan tó ń jẹ́ Símónì.+

10 Ọkùnrin kan wà ní Kesaríà tó ń jẹ́ Kọ̀nílíù, ọ̀gá ọmọ ogun* kan nínú àwùjọ tí wọ́n ń pè ní àwùjọ Ítálì.* 2 Onífọkànsìn tó bẹ̀rù Ọlọ́run ni òun àti gbogbo agbo ilé rẹ̀, ó ń fún àwọn èèyàn ní ọ̀pọ̀ ọrẹ àánú, ó sì máa ń rawọ́ ẹ̀bẹ̀ sí Ọlọ́run nígbà gbogbo. 3 Ní nǹkan bí wákàtí kẹsàn-án+ ọjọ́,* ó rí áńgẹ́lì Ọlọ́run kedere nínú ìran, tí ó wọlé wá bá a, ó sì sọ pé: “Kọ̀nílíù!” 4 Kọ̀nílíù tẹjú mọ́ ọn, ẹ̀rù ń bà á, ó sì bi í pé: “Ṣé kò sí o, Olúwa?” Ó sọ fún un pé: “Àwọn àdúrà àti àwọn ọrẹ àánú rẹ ti dé iwájú Ọlọ́run, ó sì ti mú kó rántí rẹ.+ 5 Nítorí náà, rán àwọn èèyàn sí Jópà, kí o sì ní kí wọ́n pe ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Símónì, tí wọ́n tún ń pè ní Pétérù wá. 6 Ọkùnrin yìí ni àlejò tó wà* lọ́dọ̀ Símónì, oníṣẹ́ awọ, tó ní ilé sétí òkun.” 7 Gbàrà tí áńgẹ́lì tó bá a sọ̀rọ̀ lọ, ó pe méjì lára àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ àti ọmọ ogun kan tó jẹ́ onífọkànsìn lára àwọn tó ń ṣèránṣẹ́ fún un, 8 ó sọ gbogbo ohun tó ṣẹlẹ̀ fún wọn, ó sì rán wọn lọ sí Jópà.

9 Lọ́jọ́ kejì, bí wọ́n ṣe ń bá ìrìn àjò wọn lọ, tí wọ́n sì ń sún mọ́ ìlú náà, Pétérù lọ sórí ilé ní nǹkan bíi wákàtí kẹfà* láti gbàdúrà. 10 Àmọ́ ebi bẹ̀rẹ̀ sí í pa á gan-an, ó sì fẹ́ jẹun. Bí wọ́n ṣe ń ṣe oúnjẹ lọ́wọ́, ó bọ́ sójú ìran,+ 11 ó rí i tí ọ̀run ṣí sílẹ̀, ohun kan* sì ń sọ̀ kalẹ̀ tó dà bí aṣọ ọ̀gbọ̀ fífẹ̀ tí wọ́n ń fi àwọn igun rẹ̀ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin sọ̀ ọ́ kalẹ̀ sí ayé; 12 oríṣiríṣi ẹranko ẹlẹ́sẹ̀ mẹ́rin àti àwọn ẹran tó ń fàyà fà* lórí ilẹ̀ pẹ̀lú àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run ló wà nínú rẹ̀. 13 Lẹ́yìn náà, ohùn kan sọ fún un pé: “Dìde, Pétérù, máa pa, kí o sì máa jẹ!” 14 Àmọ́ Pétérù sọ pé: “Rárá o, Olúwa, mi ò jẹ ohunkóhun tó jẹ́ ẹlẹ́gbin tàbí aláìmọ́ rí.”+ 15 Ohùn náà tún sọ fún un lẹ́ẹ̀kejì pé: “Yéé pe ohun tí Ọlọ́run ti wẹ̀ mọ́ ní ẹlẹ́gbin.” 16 Èyí ṣẹlẹ̀ nígbà kẹta, lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, a gbé e* lọ sí ọ̀run.

17 Nígbà tí Pétérù ṣì ń ṣe kàyéfì nípa ohun tí ìran tó rí túmọ̀ sí, àwọn ọkùnrin tí Kọ̀nílíù rán níṣẹ́ wá béèrè ibi tí ilé Símónì wà, wọ́n sì dúró sí ẹnubodè.+ 18 Wọ́n nahùn sókè, wọ́n sì béèrè bóyá wọ́n gba Símónì tí wọ́n ń pè ní Pétérù lálejò níbẹ̀. 19 Bí Pétérù ṣe ń ronú nípa ìran náà lọ́wọ́, ẹ̀mí+ sọ fún un pé: “Wò ó! Àwọn ọkùnrin mẹ́ta ń béèrè rẹ. 20 Torí náà, dìde, sọ̀ kalẹ̀, kí o sì bá wọn lọ, má ṣiyèméjì rárá, nítorí èmi ni mo rán wọn wá.” 21 Pétérù bá sọ̀ kalẹ̀ lọ bá àwọn ọkùnrin náà, ó sì sọ pé: “Èmi ni ẹni tí ẹ̀ ń wá. Kí lẹ bá wá o?” 22 Wọ́n sọ pé: “Kọ̀nílíù,+ ọ̀gá ọmọ ogun, ọkùnrin kan tó jẹ́ olódodo, tó bẹ̀rù Ọlọ́run, tí gbogbo orílẹ̀-èdè Júù sì ń ròyìn rẹ̀ dáadáa, ni áńgẹ́lì mímọ́ kan fún ní àṣẹ àtọ̀runwá pé kó ránṣẹ́ pè ọ́ láti wá sí ilé òun, kí ó lè gbọ́ ohun tí o ní láti sọ.” 23 Nítorí náà, ó ní kí wọ́n wọlé, ó sì gbà wọ́n lálejò.

Lọ́jọ́ kejì, ó dìde, ó sì bá wọn lọ, lára àwọn arákùnrin tó wá láti Jópà náà bá a lọ. 24 Lọ́jọ́ tó tẹ̀ lé e, ó wọ Kesaríà. Ní ti tòótọ́, Kọ̀nílíù ti ń retí wọn, ó sì ti pe àwọn mọ̀lẹ́bí rẹ̀ àti àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ tímọ́tímọ́ jọ. 25 Bí Pétérù ṣe wọlé, Kọ̀nílíù pàdé rẹ̀, ó kúnlẹ̀ síbi ẹsẹ̀ rẹ̀, ó sì tẹrí ba* fún un. 26 Àmọ́ Pétérù gbé e dìde, ó sọ pé: “Dìde; èèyàn lèmi náà.”+ 27 Bí ó ṣe ń bá a sọ̀rọ̀, ó wọlé, ó sì rí ọ̀pọ̀ èèyàn tí wọ́n pé jọ. 28 Ó sọ fún wọn pé: “Ẹ̀yin náà mọ̀ dáadáa pé kò bófin mu rárá fún Júù láti dara pọ̀ mọ́ ẹnikẹ́ni tó bá wá láti orílẹ̀-èdè míì tàbí kó wá sọ́dọ̀ rẹ̀,+ síbẹ̀ Ọlọ́run fi hàn mí pé kí n má ṣe pe èèyàn kankan ní ẹlẹ́gbin tàbí aláìmọ́.+ 29 Nítorí náà, mo wá láìjanpata nígbà tí wọ́n ránṣẹ́ pè mí. Ní báyìí, mo fẹ́ mọ ìdí tí ẹ fi ránṣẹ́ pè mí.”

30 Kọ̀nílíù wá sọ pé: “Ọjọ́ mẹ́rin sẹ́yìn, tí a bá kà á láti wákàtí yìí, mò ń gbàdúrà nínú ilé mi ní wákàtí kẹsàn-án;* ni ọkùnrin kan tó wọ aṣọ títàn yòò bá dúró síwájú mi, 31 ó sì sọ pé: ‘Kọ̀nílíù, àdúrà rẹ ti gbà, a sì ti rántí àwọn ọrẹ àánú rẹ níwájú Ọlọ́run. 32 Torí náà, ránṣẹ́ sí Jópà, kí o sì pe Símónì tí wọ́n ń pè ní Pétérù wá. Ọkùnrin yìí jẹ́ àlejò ní ilé Símónì, oníṣẹ́ awọ, létí òkun.’+ 33 Nítorí náà, mo ránṣẹ́ sí ọ ní kíá, o sì ṣe dáadáa bí o ṣe wá síbí. Ní báyìí, gbogbo wa wà níwájú Ọlọ́run láti gbọ́ gbogbo ohun tí Jèhófà* ti pàṣẹ pé kí o sọ.”

34 Ni Pétérù bá bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀, ó ní: “Ní báyìí, ó ti wá yé mi dáadáa pé Ọlọ́run kì í ṣe ojúsàájú,+ 35 àmọ́ ní gbogbo orílẹ̀-èdè, ẹni tó bá bẹ̀rù rẹ̀, tó sì ń ṣe ohun tí ó tọ́ ni ẹni ìtẹ́wọ́gbà lọ́dọ̀ rẹ̀.+ 36 Ó ránṣẹ́ sí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kí ó lè kéde ìhìn rere àlàáfíà+ fún wọn nípasẹ̀ Jésù Kristi, ẹni yìí ni Olúwa gbogbo èèyàn.+ 37 Ẹ mọ ọ̀rọ̀ tí wọ́n ń sọ nípa rẹ̀ káàkiri gbogbo Jùdíà, bẹ̀rẹ̀ láti Gálílì+ lẹ́yìn ìrìbọmi tí Jòhánù wàásù: 38 nípa Jésù tó wá láti Násárẹ́tì, bí Ọlọ́run ṣe fi ẹ̀mí mímọ́+ àti agbára yàn án, tí ó sì lọ káàkiri ilẹ̀ náà, tí ó ń ṣe rere, tí ó sì ń wo gbogbo àwọn tí Èṣù ń ni lára sàn,+ torí pé Ọlọ́run wà pẹ̀lú rẹ̀.+ 39 Àwa sì ni ẹlẹ́rìí gbogbo ohun tí ó ṣe ní ilẹ̀ àwọn Júù àti ní Jerúsálẹ́mù; àmọ́ wọ́n pa á bí wọ́n ṣe gbé e kọ́ sórí òpó igi.* 40 Ọlọ́run jí ẹni yìí dìde ní ọjọ́ kẹta,+ ó sì jẹ́ kó fara hàn kedere,* 41 kì í ṣe fún gbogbo èèyàn, bí kò ṣe fún àwọn ẹlẹ́rìí tí Ọlọ́run ti yàn ṣáájú, fún àwa, tí a bá a jẹ, tí a sì bá a mu lẹ́yìn tí ó dìde kúrò nínú ikú.+ 42 Bákan náà, ó pàṣẹ fún wa pé ká wàásù fún àwọn èèyàn ká sì jẹ́rìí kúnnákúnná+ pé ẹni yìí ni Ọlọ́run pàṣẹ pé kí ó jẹ́ onídàájọ́ alààyè àti òkú.+ 43 Òun ni gbogbo àwọn wòlíì jẹ́rìí sí,+ pé gbogbo ẹni tó bá gbà á gbọ́ máa rí ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ gbà nípasẹ̀ orúkọ rẹ̀.”+

44 Nígbà tí Pétérù ṣì ń sọ̀rọ̀ lọ́wọ́ nípa nǹkan yìí, ẹ̀mí mímọ́ bà lé gbogbo àwọn tó ń gbọ́ ọ̀rọ̀ náà.+ 45 Ẹnu ya àwọn onígbàgbọ́* tó ti dádọ̀dọ́* tí wọ́n bá Pétérù wá, torí pé ẹ̀bùn ọ̀fẹ́ ẹ̀mí mímọ́ tú jáde sórí àwọn èèyàn orílẹ̀-èdè pẹ̀lú. 46 Nítorí wọ́n gbọ́ tí wọ́n ń sọ àwọn èdè àjèjì,* tí wọ́n sì ń gbé Ọlọ́run ga.+ Nígbà náà, Pétérù dáhùn pé: 47 “Ṣé ẹnikẹ́ni lè sọ pé ká má fi omi batisí àwọn èèyàn yìí,+ àwọn tó ti gba ẹ̀mí mímọ́ bí àwa náà ṣe gbà á?” 48 Nítorí náà, ó pàṣẹ pé kí a batisí wọn ní orúkọ Jésù Kristi.+ Lẹ́yìn náà, wọ́n ní kó lo ọjọ́ díẹ̀ lọ́dọ̀ àwọn.

11 Àwọn àpọ́sítélì àti àwọn ará tó wà ní Jùdíà gbọ́ pé àwọn èèyàn orílẹ̀-èdè pẹ̀lú ti gba ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. 2 Torí náà, nígbà tí Pétérù wá sí Jerúsálẹ́mù, àwọn tó ń ti ọ̀rọ̀ ìdádọ̀dọ́*+ lẹ́yìn bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàríwísí rẹ̀,* 3 wọ́n sọ pé: “O wọ ilé àwọn tí kò dádọ̀dọ́,* o sì bá wọn jẹun.” 4 Ni Pétérù bá bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàlàyé kúlẹ̀kúlẹ̀ ọ̀rọ̀ náà fún wọn, ó ní:

5 “Ìlú Jópà ni mo wà tí mo ti ń gbàdúrà, mo sì rí ìran kan nígbà tí mo wà lójú ìran, ohun* kan ń sọ̀ kalẹ̀ bọ̀ bí aṣọ ọ̀gbọ̀ fífẹ̀ tí a fi igun rẹ̀ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin sọ̀ ọ́ kalẹ̀ láti ọ̀run, ó sì wá tààrà sọ́dọ̀ mi.+ 6 Bí mo ṣe tẹjú mọ́ ọn, mo rí àwọn ẹranko ẹlẹ́sẹ̀ mẹ́rin orí ilẹ̀, àwọn ẹran inú igbó, àwọn ẹran tó ń fàyà fà* àti àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run. 7 Mo tún gbọ́ ohùn kan tó sọ fún mi pé: ‘Dìde, Pétérù, máa pa, kí o sì máa jẹ!’ 8 Àmọ́ mo sọ pé: ‘Rárá o, Olúwa, torí ohun tó jẹ́ ẹlẹ́gbin tàbí aláìmọ́ kò wọ ẹnu mi rí.’ 9 Nígbà kejì, ohùn tó wá láti ọ̀run náà sọ pé: ‘Yéé pe àwọn ohun tí Ọlọ́run ti wẹ̀ mọ́ ní ẹlẹ́gbin.’ 10 Èyí ṣẹlẹ̀ nígbà kẹta, a sì fa gbogbo rẹ̀ pa dà sókè ọ̀run. 11 Ní àkókò yẹn náà, àwọn ọkùnrin mẹ́ta dúró níwájú ilé tí a wà, wọ́n rán wọn sí mi láti Kesaríà.+ 12 Ni ẹ̀mí bá sọ fún mi pé kí n bá wọn lọ láìṣiyèméjì rárá. Àwọn arákùnrin mẹ́fà yìí náà bá mi lọ, a sì wọ ilé ọkùnrin náà.

13 “Ó ròyìn fún wa bí ó ṣe rí áńgẹ́lì tó dúró ní ilé rẹ̀ tó sì sọ pé: ‘Rán àwọn èèyàn sí Jópà, kí o sì ní kí wọ́n pe Símónì tí wọ́n ń pè ní Pétérù wá,+ 14 yóò sọ ohun tó máa mú kí ìwọ àti gbogbo agbo ilé rẹ rí ìgbàlà.’ 15 Àmọ́ nígbà tí mo bẹ̀rẹ̀ sí í sọ̀rọ̀, ẹ̀mí mímọ́ bà lé wọn bó ṣe bà lé wa ní ìbẹ̀rẹ̀.+ 16 Ni mo bá rántí ọ̀rọ̀ tí Olúwa máa ń sọ, pé: ‘Jòhánù fi omi batisí,+ àmọ́ a ó fi ẹ̀mí mímọ́ batisí yín.’+ 17 Torí náà, tí Ọlọ́run bá fún wọn ní ẹ̀bùn ọ̀fẹ́ kan náà tí ó fún àwa tí a ti gba Jésù Kristi Olúwa gbọ́, ta ni èmi tí màá fi dí Ọlọ́run lọ́wọ́?”*+

18 Nígbà tí wọ́n gbọ́ àwọn nǹkan yìí, wọn ò ta kò ó mọ́,* wọ́n sì yin Ọlọ́run lógo, pé: “Tóò, Ọlọ́run ti fún àwọn èèyàn orílẹ̀-èdè láǹfààní láti ronú pìwà dà kí àwọn náà lè ní ìyè.”+

19 Nígbà náà, àwọn tí ìpọ́njú tó wáyé nítorí Sítéfánù mú kí wọ́n tú ká+ ń lọ títí dé Foníṣíà, Sápírọ́sì àti Áńtíókù, àmọ́ àwọn Júù nìkan ni wọ́n ń wàásù fún.+ 20 Síbẹ̀, àwọn kan lára wọn tó wá láti Sápírọ́sì àti Kírénè wá sí Áńtíókù, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í bá àwọn tó ń sọ èdè Gíríìkì sọ̀rọ̀, wọ́n ń kéde ìhìn rere Jésù Olúwa. 21 Yàtọ̀ síyẹn, ọwọ́ Jèhófà* wà lára wọn, ọ̀pọ̀ èèyàn di onígbàgbọ́, wọ́n sì yíjú sí Olúwa.+

22 Ìròyìn nípa wọn dé ìjọ tó wà ní Jerúsálẹ́mù, wọ́n sì rán Bánábà+ lọ títí dé Áńtíókù. 23 Nígbà tó dé, tó sì rí inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Ọlọ́run, inú rẹ̀ dùn, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í fún gbogbo wọn ní ìṣírí láti máa fi gbogbo ọkàn wọn ṣègbọràn sí Olúwa;+ 24 èèyàn rere ni, ó sì kún fún ẹ̀mí mímọ́ àti ìgbàgbọ́. Torí náà, ọ̀pọ̀ èèyàn dara pọ̀ mọ́ Olúwa.+ 25 Nítorí náà, ó lọ sí Tásù láti wá Sọ́ọ̀lù kàn.+ 26 Lẹ́yìn tó rí i, ó mú un wá sí Áńtíókù. Odindi ọdún kan ni wọ́n fi ń pé jọ pẹ̀lú àwọn ará nínú ìjọ, wọ́n sì kọ́ ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn, Áńtíókù ni Ọlọ́run ti kọ́kọ́ mú kí á máa pe àwọn ọmọ ẹ̀yìn ní Kristẹni.+

27 Ní àkókò yẹn, àwọn wòlíì+ wá láti Jerúsálẹ́mù sí Áńtíókù. 28 Ọ̀kan lára wọn tó ń jẹ́ Ágábù + dìde, ó sì sọ tẹ́lẹ̀ nípasẹ̀ ẹ̀mí pé ìyàn ńlá máa tó mú ní gbogbo ilẹ̀ ayé+ tí à ń gbé, èyí sì ṣẹlẹ̀ lóòótọ́ lásìkò Kíláúdíù. 29 Torí náà, àwọn ọmọ ẹ̀yìn pinnu, gẹ́gẹ́ bí ohun tí agbára kálukú wọn gbé,+ láti fi nǹkan ìrànwọ́*+ ránṣẹ́ sí àwọn ará tó ń gbé ní Jùdíà; 30 ohun tí wọ́n sì ṣe nìyẹn, wọ́n fi rán Bánábà àti Sọ́ọ̀lù sí àwọn alàgbà.+

12 Ní àkókò yẹn, Ọba Hẹ́rọ́dù bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe inúnibíni sí àwọn kan nínú ìjọ.+ 2 Ó fi idà+ pa Jémíìsì arákùnrin Jòhánù.+ 3 Nígbà tó rí i pé ó dùn mọ́ àwọn Júù nínú, ó tún lọ mú Pétérù. (Èyí ṣẹlẹ̀ nígbà àjọyọ̀ Búrẹ́dì Aláìwú.)+ 4 Ó gbá a mú, ó fi í sẹ́wọ̀n,+ ó sì fi í sábẹ́ ọ̀wọ́ mẹ́rin àwọn oníṣẹ́ àṣegbà tí ọ̀wọ́ kọ̀ọ̀kan ní ọmọ ogun mẹ́rin-mẹ́rin láti máa ṣọ́ ọ, ó ní in lọ́kàn láti mú un wá síwájú* àwọn èèyàn náà lẹ́yìn Ìrékọjá. 5 Nítorí náà, wọ́n fi Pétérù sínú ẹ̀wọ̀n, àmọ́ ìjọ ń gbàdúrà kíkankíkan sí Ọlọ́run nítorí rẹ̀.+

6 Nígbà tó kù díẹ̀ kí Hẹ́rọ́dù mú un jáde, ní òru yẹn, Pétérù ń sùn tòun ti ṣẹkẹ́ṣẹkẹ̀ méjì tí wọ́n fi dè é, ó wà láàárín ọmọ ogun méjì, àwọn ẹ̀ṣọ́ tó wà lẹ́nu ilẹ̀kùn sì ń ṣọ́ ilé ẹ̀wọ̀n náà. 7 Àmọ́ wò ó! Áńgẹ́lì Jèhófà* dúró síbẹ̀,+ ìmọ́lẹ̀ kan sì tàn nínú yàrá ẹ̀wọ̀n náà. Ó gbá Pétérù pẹ́pẹ́ lẹ́gbẹ̀ẹ́, ó jí i, ó sọ pé: “Dìde kíákíá!” Àwọn ṣẹkẹ́ṣẹkẹ̀ náà sì bọ́ kúrò lọ́wọ́ rẹ̀.+ 8 Áńgẹ́lì náà sọ fún un pé: “Wọ aṣọ rẹ,* kí o sì wọ bàtà rẹ.” Ó ṣe bẹ́ẹ̀. Níkẹyìn, ó sọ fún un pé: “Gbé aṣọ àwọ̀lékè rẹ wọ̀, kí o sì máa tẹ̀ lé mi.” 9 Ó jáde, ó sì ń tẹ̀ lé e, àmọ́ kò mọ̀ pé ohun tó ń ṣẹlẹ̀ látọwọ́ áńgẹ́lì náà jẹ́ ohun gidi. Àní, ṣe ló rò pé òun ń rí ìran. 10 Wọ́n kọjá ẹ̀ṣọ́ ológun kìíní àti èkejì, wọ́n dé ẹnubodè onírin tó wọnú ìlú náà, ó sì fúnra rẹ̀ ṣí fún wọn. Lẹ́yìn tí wọ́n jáde, wọ́n gba ojú ọ̀nà kan lọ, áńgẹ́lì náà sì kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀. 11 Bí Pétérù ṣe wá mọ ohun tó ń ṣẹlẹ̀, ó sọ pé: “Ní báyìí, mo ti mọ̀ dájú pé Jèhófà* ló rán áńgẹ́lì rẹ̀ láti gbà mí lọ́wọ́ Hẹ́rọ́dù àti lọ́wọ́ gbogbo ohun tí àwọn Júù ń retí pé kó ṣẹlẹ̀.”+

12 Lẹ́yìn tó ti mọ ohun tó ṣẹlẹ̀, ó lọ sí ilé Màríà ìyá Jòhánù tí wọ́n ń pè ní Máàkù,+ níbi tí àwọn díẹ̀ kóra jọ sí, tí wọ́n ń gbàdúrà. 13 Nígbà tó kan ilẹ̀kùn ẹnu ọ̀nà àbáwọlé, ìránṣẹ́bìnrin kan tó ń jẹ́ Ródà wá dá a lóhùn. 14 Nígbà tó mọ̀ pé ohùn Pétérù ni, inú rẹ̀ dùn débi pé kò ṣí ilẹ̀kùn náà, àmọ́ ó sáré wọlé, ó sì sọ fún wọn pé Pétérù ló wà lẹ́nu ọ̀nà. 15 Wọ́n sọ fún un pé: “Orí rẹ dà rú.” Àmọ́, ó ń tẹnu mọ́ ọn pé òun ni. Wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í sọ pé: “Áńgẹ́lì rẹ̀ ni.” 16 Ṣùgbọ́n Pétérù ò kúrò níbẹ̀, ó ń kan ilẹ̀kùn. Nígbà tí wọ́n ṣílẹ̀kùn, wọ́n rí i, ẹnu sì yà wọ́n. 17 Àmọ́, ó fọwọ́ sọ fún wọn pé kí wọ́n dákẹ́, ó sì sọ kúlẹ̀kúlẹ̀ bí Jèhófà* ṣe mú un jáde kúrò nínú ẹ̀wọ̀n, ó sọ pé: “Ẹ sọ àwọn nǹkan yìí fún Jémíìsì+ àti àwọn ará.” Lẹ́yìn náà, ó jáde, ó sì rin ìrìn àjò lọ sí ibòmíì.

18 Nígbà tí ilẹ̀ mọ́, arukutu sọ láàárín àwọn ọmọ ogun lórí ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Pétérù. 19 Hẹ́rọ́dù fara balẹ̀ wá a, nígbà tí kò rí i, ó da ìbéèrè bo àwọn ẹ̀ṣọ́ náà, ó sì pàṣẹ pé kí wọ́n lọ fìyà jẹ wọ́n;+ ó lọ láti Jùdíà sí Kesaríà, ó sì lo àkókò díẹ̀ níbẹ̀.

20 Inú ń bí i gidigidi* sí àwọn èèyàn Tírè àti Sídónì. Nítorí náà, wọ́n wá sọ́dọ̀ rẹ̀ pẹ̀lú èrò tó ṣọ̀kan. Lẹ́yìn tí wọ́n sì ti yí Bílásítù tó ń bójú tó ohun tó ń lọ nínú ilé ọba* lérò pa dà, wọ́n bẹ̀bẹ̀ fún àlàáfíà, nítorí ilẹ̀ ọba ló ń pèsè oúnjẹ fún ilẹ̀ wọn. 21 Lọ́jọ́ pàtàkì kan, Hẹ́rọ́dù gbé aṣọ ìgúnwà wọ̀, ó jókòó sórí ìjókòó ìdájọ́, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í sọ àsọyé fún gbogbo wọn. 22 Ni àwọn èèyàn tó pé jọ bá bẹ̀rẹ̀ sí í kígbe pé: “Ohùn ọlọ́run ni, kì í ṣe ti èèyàn!” 23 Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, áńgẹ́lì Jèhófà* kọ lù ú, nítorí kò fi ògo fún Ọlọ́run, ìdin* jẹ ẹ́, ó sì kú.

24 Àmọ́ ọ̀rọ̀ Jèhófà* ń gbilẹ̀, ó sì ń tàn kálẹ̀.+

25 Ní ti Bánábà+ àti Sọ́ọ̀lù, lẹ́yìn tí wọ́n ti parí gbogbo iṣẹ́ ìrànwọ́ tí wọ́n ń ṣe ní Jerúsálẹ́mù,+ wọ́n pa dà, wọ́n sì mú Jòhánù+ tí wọ́n tún ń pè ní Máàkù dání.

13 Ní Áńtíókù, àwọn wòlíì àti àwọn olùkọ́ wà nínú ìjọ tó wà níbẹ̀,+ àwọn ni: Bánábà, Símíónì tí wọ́n ń pè ní Nígérì, Lúkíọ́sì ará Kírénè àti Mánáénì tó kẹ́kọ̀ọ́ lọ́dọ̀ Hẹ́rọ́dù alákòóso agbègbè náà, àti Sọ́ọ̀lù. 2 Bí wọ́n ṣe ń ṣiṣẹ́ Jèhófà,* tí wọ́n sì ń gbààwẹ̀, ẹ̀mí mímọ́ sọ pé: “Ẹ ya Bánábà àti Sọ́ọ̀lù+ sọ́tọ̀ fún mi kí wọ́n lè ṣe iṣẹ́ tí mo pè wọ́n sí.”+ 3 Lẹ́yìn tí wọ́n gbààwẹ̀, tí wọ́n sì gbàdúrà, wọ́n gbé ọwọ́ lé wọn, wọ́n sì rán wọn lọ.

4 Torí náà, àwọn ọkùnrin tí ẹ̀mí mímọ́ rán jáde yìí lọ sí Séléúkíà, wọ́n sì wọkọ̀ láti ibẹ̀ lọ sí Sápírọ́sì. 5 Nígbà tí wọ́n dé Sálámísì, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í kéde ọ̀rọ̀ Ọlọ́run nínú àwọn sínágọ́gù àwọn Júù. Jòhánù sì wà lọ́dọ̀ wọn, ó ń ṣe ìránṣẹ́.*+

6 Nígbà tí wọ́n ti gba gbogbo erékùṣù náà kọjá títí dé Páfò, wọ́n bá ọkùnrin Júù kan pàdé tó ń jẹ́ Baa-Jésù, oníṣẹ́ oṣó àti wòlíì èké ni. 7 Ó wà pẹ̀lú Sájíọ́sì Pọ́lọ́sì tó jẹ́ alákòóso ìbílẹ̀,* ọkùnrin onílàákàyè ni. Ọkùnrin yìí pe Bánábà àti Sọ́ọ̀lù wá sọ́dọ̀ ara rẹ̀, ara rẹ̀ ti wà lọ́nà láti gbọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. 8 Àmọ́ Élímà oníṣẹ́ oṣó náà (torí bí wọ́n ṣe túmọ̀ orúkọ rẹ̀ nìyẹn) bẹ̀rẹ̀ sí í ta kò wọ́n, ó fẹ́ yí alákòóso ìbílẹ̀ náà kúrò nínú ẹ̀kọ́ ìgbàgbọ́. 9 Ni Sọ́ọ̀lù, tí wọ́n tún ń pè ní Pọ́ọ̀lù, ẹni tó ti kún fún ẹ̀mí mímọ́, bá tẹjú mọ́ ọn, 10 ó sì sọ pé: “Ìwọ ọkùnrin tí oríṣiríṣi jìbìtì àti ìwà ibi kún ọwọ́ rẹ̀, ìwọ ọmọ Èṣù,+ ìwọ ọ̀tá gbogbo ohun tó jẹ́ òdodo, ṣé o kò ní ṣíwọ́ yíyí àwọn ọ̀nà títọ́ Jèhófà* po ni? 11 Wò ó! Ọwọ́ Jèhófà* wà lára rẹ, wàá fọ́ lójú, o ò ní rí ìmọ́lẹ̀ oòrùn fún àkókò kan.” Lójú ẹsẹ̀, kùrukùru tó ṣú àti òkùnkùn bò ó, ó sì ń táràrà, ó ń wá ẹni tó máa di òun lọ́wọ́ mú lọ. 12 Bí alákòóso ìbílẹ̀ náà ṣe rí ohun tó ṣẹlẹ̀, ó di onígbàgbọ́, torí ẹ̀kọ́ Jèhófà* yà á lẹ́nu gan-an.

13 Nígbà náà, Pọ́ọ̀lù àti àwọn alábàákẹ́gbẹ́ rẹ̀ wọ ọkọ̀ òkun láti Páfò, wọ́n sì dé Pẹ́gà ní Panfílíà. Àmọ́ Jòhánù+ fi wọ́n sílẹ̀, ó sì pa dà sí Jerúsálẹ́mù.+ 14 Àmọ́, wọ́n tẹ̀ síwájú láti Pẹ́gà, wọ́n sì wá sí Áńtíókù ní Písídíà. Wọ́n wọ sínágọ́gù+ ní ọjọ́ Sábáàtì, wọ́n sì jókòó. 15 Lẹ́yìn kíka Òfin+ àti ìwé àwọn Wòlíì fún àwọn èèyàn, àwọn alága sínágọ́gù ránṣẹ́ sí wọn, pé: “Ẹ̀yin èèyàn, ẹ̀yin ará, tí ẹ bá ní ọ̀rọ̀ ìṣírí èyíkéyìí fún àwọn èèyàn, ẹ sọ ọ́.” 16 Ni Pọ́ọ̀lù bá dìde, ó sì ń fọwọ́ ṣàpèjúwe, ó sọ pé:

“Ẹ̀yin èèyàn, ẹ̀yin ọmọ Ísírẹ́lì àti ẹ̀yin yòókù tí ẹ bẹ̀rù Ọlọ́run, ẹ fetí sílẹ̀. 17 Ọlọ́run àwọn èèyàn Ísírẹ́lì yìí yan àwọn baba ńlá wa, ó gbé àwọn èèyàn náà ga nígbà tí wọ́n jẹ́ àjèjì ní ilẹ̀ Íjíbítì, ó sì fi ọwọ́ agbára* mú wọn jáde kúrò níbẹ̀.+ 18 Nǹkan bí ogójì (40) ọdún ló fi fara dà á fún wọn ní aginjù.+ 19 Lẹ́yìn tó pa orílẹ̀-èdè méje run ní ilẹ̀ Kénáánì, ó fi ilẹ̀ wọn ṣe ogún fún àwọn baba ńlá wa.+ 20 Gbogbo èyí wáyé láàárín nǹkan bí ọgọ́rùn-ún mẹ́rin ó lé àádọ́ta (450) ọdún.

“Lẹ́yìn náà, ó fún wọn ní àwọn onídàájọ́ títí di ìgbà wòlíì Sámúẹ́lì.+ 21 Àmọ́ nígbà tó yá, wọ́n ní àwọn fẹ́ ọba,+ Ọlọ́run sì fún wọn ní Sọ́ọ̀lù ọmọ Kíṣì, ọkùnrin kan látinú ẹ̀yà Bẹ́ńjámínì,+ ó fi ogójì (40) ọdún jọba. 22 Lẹ́yìn tó mú un kúrò, ó gbé Dáfídì dìde láti jẹ́ ọba wọn,+ ẹni tó jẹ́rìí nípa rẹ̀, tó sì sọ pé: ‘Mo ti rí Dáfídì ọmọ Jésè,+ ẹni tí ọkàn mi fẹ́;+ yóò ṣe gbogbo ohun tí mo fẹ́.’ 23 Gẹ́gẹ́ bí ìlérí tó ṣe, látọ̀dọ̀ ọmọ* ọkùnrin yìí ni Ọlọ́run ti mú olùgbàlà wá fún Ísírẹ́lì, ìyẹn Jésù.+ 24 Kí ẹni yẹn tó dé, Jòhánù ti wàásù ní gbangba fún gbogbo èèyàn Ísírẹ́lì nípa ìrìbọmi tó jẹ́ àmì ìrònúpìwàdà.+ 25 Àmọ́ bí Jòhánù ṣe ń parí iṣẹ́ rẹ̀ lọ, ó ń sọ pé: ‘Ta ni ẹ rò pé mo jẹ́? Èmi kọ́ ni ẹni náà. Àmọ́, ẹ wò ó! Ẹnì kan ń bọ̀ lẹ́yìn mi tí mi ò tó bàtà ẹsẹ̀ rẹ̀ tú.’+

26 “Ẹ̀yin èèyàn, ẹ̀yin ará, ẹ̀yin àtọmọdọ́mọ ìdílé Ábúráhámù àti àwọn yòókù láàárín yín tó bẹ̀rù Ọlọ́run, a ti fi ọ̀rọ̀ ìgbàlà yìí ránṣẹ́ sí wa.+ 27 Àwọn tó ń gbé Jerúsálẹ́mù àti àwọn alákòóso wọn kò dá ẹni yìí mọ̀, àmọ́ nígbà tí wọ́n ń ṣiṣẹ́ onídàájọ́, wọ́n mú àwọn ohun tí àwọn Wòlíì sọ ṣẹ,+ èyí tí à ń kà sókè ní gbogbo sábáàtì. 28 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọn kò rí ìdí kankan tó fi jẹ̀bi ikú,+ wọ́n ní kí Pílátù jẹ́ kí wọ́n pa á.+ 29 Nígbà tí wọ́n ti mú gbogbo ohun tó wà lákọsílẹ̀ nípa rẹ̀ ṣẹ, wọ́n gbé e sọ̀ kalẹ̀ lórí òpó igi,* wọ́n sì tẹ́ ẹ sínú ibojì.*+ 30 Àmọ́ Ọlọ́run gbé e dìde kúrò nínú ikú,+ 31 ọjọ́ púpọ̀ ni àwọn tó bá a lọ láti Gálílì sí Jerúsálẹ́mù fi rí i. Àwọn yìí ló wá ń jẹ́rìí nípa rẹ̀ fún àwọn èèyàn.+

32 “Nítorí náà, ìhìn rere nípa ìlérí tí Ọlọ́run ṣe fún àwọn baba ńlá wa là ń kéde fún yín. 33 Ọlọ́run ti mú un ṣẹ pátápátá fún àwa ọmọ wọn bó ṣe jí Jésù dìde;+ gẹ́gẹ́ bí ó ṣe wà lákọsílẹ̀ nínú sáàmù kejì pé: ‘Ìwọ ni ọmọ mi, òní ni mo di bàbá rẹ.’+ 34 Bí Ó ṣe jí i dìde nínú ikú, tí kò sì jẹ́ kó pa dà sí ara tó lè díbàjẹ́ mọ́, ó sọ ọ́ lọ́nà yìí pé: ‘Màá fi ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ tí mo ṣèlérí fún Dáfídì hàn sí ọ, èyí tó jẹ́ òtítọ́.’*+ 35 Bákan náà, ó tún wà nínú sáàmù míì pé: ‘O ò ní jẹ́ kí ẹni ìdúróṣinṣin rẹ rí ìdíbàjẹ́.’+ 36 Dáfídì ní tirẹ̀ ṣe iṣẹ́ ìsìn fún* Ọlọ́run ní ìran rẹ̀, ó sùn nínú ikú, wọ́n sin ín pẹ̀lú àwọn baba ńlá rẹ̀, ó sì rí ìdíbàjẹ́.+ 37 Àmọ́, ẹni tí Ọlọ́run gbé dìde kò rí ìdíbàjẹ́.+

38 “Nítorí náà, ẹ̀yin ará, ẹ jẹ́ kó yé yín pé ipasẹ̀ ẹni yìí la fi ń kéde ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ fún yín,+ 39 àti pé nínú gbogbo ohun tí a kò lè sọ pé ẹ ò jẹ̀bi rẹ̀ nípasẹ̀ Òfin Mósè,+ ni à ń tipasẹ̀ ẹni yìí pe gbogbo ẹni tó bá gbà gbọ́ ní aláìlẹ́bi.+ 40 Nítorí náà, ẹ ṣọ́ra kí ohun tí a sọ nínú ìwé àwọn Wòlíì má bàa ṣẹ sí yín lára, pé: 41 ‘Ẹ wò ó, ẹ̀yin pẹ̀gànpẹ̀gàn, kí ẹnu yà yín, kí ẹ sì ṣègbé, nítorí mò ń ṣe iṣẹ́ kan lásìkò yín, iṣẹ́ tí ẹ ò ní gbà gbọ́ láé bí ẹnì kan bá tiẹ̀ sọ kúlẹ̀kúlẹ̀ rẹ̀ fún yín.’”+

42 Nígbà tí wọ́n ń jáde lọ, àwọn èèyàn bẹ̀ wọ́n pé kí wọ́n wá sọ nípa ọ̀rọ̀ yìí ní Sábáàtì tó tẹ̀ lé e. 43 Torí náà, lẹ́yìn tí àpéjọ sínágọ́gù parí, ọ̀pọ̀ àwọn Júù àti àwọn aláwọ̀ṣe* tí wọ́n ń sin Ọlọ́run tẹ̀ lé Pọ́ọ̀lù àti Bánábà, bí àwọn yìí sì ṣe ń bá wọn sọ̀rọ̀, wọ́n rọ̀ wọ́n pé kí wọ́n má ṣe kúrò nínú inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Ọlọ́run.+

44 Ní Sábáàtì tó tẹ̀ lé e, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ gbogbo ìlú náà ló kóra jọ láti gbọ́ ọ̀rọ̀ Jèhófà.* 45 Nígbà tí àwọn Júù rí ọ̀pọ̀ èèyàn, inú bí wọn* gidigidi, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í fi ọ̀rọ̀ òdì ta ko àwọn ohun tí Pọ́ọ̀lù ń sọ.+ 46 Ni Pọ́ọ̀lù àti Bánábà bá fi ìgboyà sọ fún wọn pé: “Ó pọn dandan pé ẹ̀yin ni kí a kọ́kọ́ sọ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fún.+ Nígbà tí ẹ sì ti kọ̀ ọ́, tí ẹ ò ka ara yín sí ẹni tó yẹ fún ìyè àìnípẹ̀kun, torí náà, a yíjú sí àwọn orílẹ̀-èdè.+ 47 Nítorí Jèhófà* ti pa àwọn ọ̀rọ̀ yìí láṣẹ fún wa pé: ‘Mo ti yàn ọ́ ṣe ìmọ́lẹ̀ àwọn orílẹ̀-èdè, kí o lè jẹ́ ìgbàlà fún gbogbo ayé.’”+

48 Nígbà tí àwọn èèyàn orílẹ̀-èdè gbọ́ èyí, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í yọ̀, wọ́n sì ń yin ọ̀rọ̀ Jèhófà* lógo, gbogbo àwọn olóòótọ́ ọkàn tí wọ́n ń fẹ́ ìyè àìnípẹ̀kun sì di onígbàgbọ́. 49 Yàtọ̀ síyẹn, ọ̀rọ̀ Jèhófà* ń gbilẹ̀ ní gbogbo ilẹ̀ náà. 50 Àmọ́ àwọn Júù ru àwọn obìnrin olókìkí tó bẹ̀rù Ọlọ́run àti àwọn ọkùnrin sàràkí-sàràkí ìlú náà sókè, wọ́n gbé inúnibíni+ dìde sí Pọ́ọ̀lù àti Bánábà, wọ́n sì jù wọ́n sí ẹ̀yìn ààlà ìlú wọn. 51 Torí náà, wọ́n gbọn ekuru ẹsẹ̀ wọn dà nù sí wọn, wọ́n sì lọ sí Íkóníónì.+ 52 Àwọn ọmọ ẹ̀yìn sì ń ní ìdùnnú+ àti ẹ̀mí mímọ́ ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́.

14 Ní Íkóníónì, wọ́n jọ wọ sínágọ́gù àwọn Júù, wọ́n sì sọ̀rọ̀ lọ́nà tó mú kí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn Júù àti Gíríìkì di onígbàgbọ́. 2 Àmọ́ àwọn Júù tí kò gbà gbọ́ ru àwọn èèyàn* orílẹ̀-èdè sókè, wọ́n sì sún wọn láti kórìíra àwọn arákùnrin.+ 3 Nítorí náà, wọ́n lo ọ̀pọ̀ àkókò láti fi ìgboyà sọ̀rọ̀ nípasẹ̀ àṣẹ Jèhófà,* ẹni tí ó jẹ́rìí sí ọ̀rọ̀ inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí rẹ̀ bí ó ṣe jẹ́ kí wọ́n ṣe àwọn iṣẹ́ àmì àti àwọn iṣẹ́ ìyanu.*+ 4 Síbẹ̀, àwọn èrò inú ìlú náà pín sí méjì; àwọn kan wà lẹ́yìn àwọn Júù, àwọn míì sì wà lẹ́yìn àwọn àpọ́sítélì. 5 Nígbà tí àwọn èèyàn orílẹ̀-èdè àti àwọn Júù pẹ̀lú àwọn alákòóso wọn gbìyànjú láti dójú tì wọ́n, kí wọ́n sì sọ wọ́n lókùúta,+ 6 wọ́n gbọ́ nípa rẹ̀, wọ́n sì sá lọ sí àwọn ìlú Likaóníà, Lísírà àti Déébè àti àwọn abúlé tó wà ní àyíká.+ 7 Wọ́n ń kéde ìhìn rere níbẹ̀.

8 Ní Lísírà, ọkùnrin kan wà ní ìjókòó tí ẹsẹ̀ rẹ̀ rọ. Àtìgbà tí wọ́n ti bí i ló ti yarọ, kò sì rìn rí. 9 Ọkùnrin yìí ń fetí sí Pọ́ọ̀lù bó ṣe ń sọ̀rọ̀. Bí Pọ́ọ̀lù ṣe tẹjú mọ́ ọn, tó sì rí i pé ó ní ìgbàgbọ́ pé òun lè rí ìwòsàn,+ 10 ó gbóhùn sókè pé: “Dìde lórí ẹsẹ̀ rẹ.” Ọkùnrin náà fò sókè, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í rìn.+ 11 Nígbà tí ọ̀pọ̀ èèyàn rí ohun tí Pọ́ọ̀lù ṣe, wọ́n gbé ohùn wọn sókè, wọ́n sì fi èdè Likaóníà sọ pé: “Àwọn ọlọ́run ti gbé àwọ̀ èèyàn wọ̀, wọ́n sì ti sọ̀ kalẹ̀ wá bá wa!”+ 12 Wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í pe Bánábà ní Súúsì, wọ́n sì ń pe Pọ́ọ̀lù ní Hẹ́mísì, torí òun ló máa ń sọ̀rọ̀ jù. 13 Àlùfáà Súúsì tí tẹ́ńpìlì rẹ̀ wà ní àbáwọlé ìlú náà mú àwọn akọ màlúù àti òdòdó ẹ̀yẹ* wá sí ẹnubodè, òun àti ọ̀pọ̀ èèyàn tó wà níbẹ̀ sì fẹ́ rúbọ.

14 Àmọ́, nígbà tí Bánábà àti Pọ́ọ̀lù, tí wọ́n jẹ́ àpọ́sítélì gbọ́ nípa rẹ̀, wọ́n fa ẹ̀wù wọn ya, wọ́n bẹ́ sáàárín èrò náà, wọ́n sì ké jáde pé: 15 “Ẹ̀yin èèyàn, kí ló dé tí ẹ̀ ń ṣe àwọn nǹkan yìí? Èèyàn bíi tiyín ni wá, àwa náà ní àwọn àìlera tí ẹ ní.+ Ìhìn rere ni à ń kéde fún yín, kí ẹ lè yí pa dà kúrò nínú àwọn ohun asán yìí sọ́dọ̀ Ọlọ́run alààyè, ẹni tó dá ọ̀run àti ayé àti òkun pẹ̀lú gbogbo ohun tó wà nínú wọn.+ 16 Ní àwọn ìran tó ti kọjá, ó gba gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè láyè láti máa ṣe bó ṣe wù wọ́n,+ 17 bó tilẹ̀ jẹ́ pé, kò ṣàìfi ẹ̀rí irú ẹni tí òun jẹ́ hàn+ ní ti pé ó ń ṣe rere, ó ń rọ òjò fún yín láti ọ̀run, ó sì ń fún yín ní àwọn àsìkò tí irè oko ń jáde,+ ó ń fi oúnjẹ bọ́ yín, ó sì ń fi ayọ̀ kún ọkàn yín.”+ 18 Pẹ̀lú gbogbo ohun tí wọ́n sọ yìí, wọ́n fẹ́rẹ̀ẹ́ má lè dá àwọn èrò náà dúró pé kí wọ́n má ṣe rúbọ sí àwọn.

19 Àmọ́ àwọn Júù dé láti Áńtíókù àti Íkóníónì, wọ́n sì yí àwọn èrò náà lọ́kàn pa dà,+ wọ́n bá sọ Pọ́ọ̀lù lókùúta, wọ́n sì wọ́ ọ sẹ́yìn òde ìlú, wọ́n rò pé ó ti kú.+ 20 Àmọ́ nígbà tí àwọn ọmọ ẹ̀yìn yí i ká, ó dìde, ó sì wọ ìlú náà. Ní ọjọ́ kejì, òun àti Bánábà lọ sí Déébè.+ 21 Lẹ́yìn tí wọ́n kéde ìhìn rere fún ìlú yẹn, tí wọ́n sì sọ àwọn díẹ̀ di ọmọ ẹ̀yìn, wọ́n pa dà sí Lísírà, Íkóníónì àti Áńtíókù. 22 Nígbà tí wọ́n débẹ̀, wọ́n fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn* lókun,+ wọ́n fún wọn ní ìṣírí láti má ṣe kúrò nínú ìgbàgbọ́, wọ́n sì sọ pé: “A gbọ́dọ̀ ti inú ọ̀pọ̀ ìpọ́njú wọ Ìjọba Ọlọ́run.”+ 23 Yàtọ̀ síyẹn, wọ́n yan àwọn alàgbà fún wọn nínú ìjọ kọ̀ọ̀kan,+ wọ́n gbàdúrà pẹ̀lú ààwẹ̀,+ wọ́n sì fà wọ́n lé Jèhófà* lọ́wọ́, ẹni tí wọ́n ní ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀.

24 Lẹ́yìn náà, wọ́n gba Písídíà kọjá, wọ́n sì wá sí Panfílíà,+ 25 lẹ́yìn tí wọ́n kéde ọ̀rọ̀ náà ní Pẹ́gà, wọ́n lọ sí Atalíà. 26 Láti ibẹ̀, wọ́n wọkọ̀ òkun lọ sí Áńtíókù, níbi tí àwọn ará ti fi wọ́n lé Ọlọ́run lọ́wọ́ pé kó fi inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí hàn sí wọn kí wọ́n lè ṣe iṣẹ́ tí wọ́n ti wá parí báyìí.+

27 Nígbà tí wọ́n dé, tí wọ́n sì kó ìjọ jọ, wọ́n ròyìn ọ̀pọ̀ ohun tí Ọlọ́run ti ṣe nípasẹ̀ wọn àti pé ó ti ṣí ilẹ̀kùn fún àwọn orílẹ̀-èdè láti di onígbàgbọ́.+ 28 Nítorí náà, wọ́n lo àkókò tó pọ̀ díẹ̀ pẹ̀lú àwọn ọmọ ẹ̀yìn.

15 Àwọn ọkùnrin kan wá láti Jùdíà, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ àwọn ará pé: “Láìjẹ́ pé ẹ dádọ̀dọ́* gẹ́gẹ́ bí àṣà tí Mósè fi lélẹ̀,+ ẹ ò lè rí ìgbàlà.” 2 Àmọ́ lẹ́yìn tí Pọ́ọ̀lù àti Bánábà ti bá wọn jiyàn díẹ̀, tí wọ́n sì jọ ṣe awuyewuye, àwọn ará ṣètò pé kí Pọ́ọ̀lù àti Bánábà pẹ̀lú àwọn míì lọ sọ́dọ̀ àwọn àpọ́sítélì àti àwọn alàgbà ní Jerúsálẹ́mù+ lórí ọ̀rọ̀* yìí.

3 Lẹ́yìn tí ìjọ ti sin àwọn ọkùnrin yìí síwájú díẹ̀, wọ́n bá ọ̀nà wọn lọ, wọ́n gba Foníṣíà àti Samáríà kọjá, wọ́n ń ròyìn ní kúlẹ̀kúlẹ̀ bí àwọn èèyàn orílẹ̀-èdè ṣe ń yí pa dà, wọ́n sì ń mú inú gbogbo àwọn ará dùn gidigidi. 4 Nígbà tí wọ́n dé Jerúsálẹ́mù, ìjọ àti àwọn àpọ́sítélì pẹ̀lú àwọn alàgbà gbà wọ́n tọwọ́tẹsẹ̀, wọ́n sì ròyìn ọ̀pọ̀ ohun tí Ọlọ́run ti ṣe nípasẹ̀ wọn. 5 Ṣùgbọ́n, àwọn kan tó wá látinú ẹ̀ya ìsìn àwọn Farisí, àmọ́ tí wọ́n ti di onígbàgbọ́ dìde lórí ìjókòó wọn, wọ́n sì sọ pé: “Ó pọn dandan kí a dádọ̀dọ́ wọn,* kí a sì pàṣẹ fún wọn pé kí wọ́n máa pa Òfin Mósè mọ́.”+

6 Torí náà, àwọn àpọ́sítélì àti àwọn alàgbà kóra jọ láti gbé ọ̀rọ̀ yìí yẹ̀ wò. 7 Lẹ́yìn ọ̀pọ̀lọpọ̀ atótónu,* Pétérù dìde, ó sì sọ fún wọn pé: “Ẹ̀yin èèyàn, ẹ̀yin ará, ẹ mọ̀ dáadáa pé tipẹ́tipẹ́ ni Ọlọ́run ti yàn mí láàárín yín pé kí àwọn èèyàn orílẹ̀-èdè kọ́kọ́ gbọ́ ìhìn rere látẹnu mi, kí wọ́n sì gbà gbọ́.+ 8 Ọlọ́run tí ó mọ ọkàn+ sì jẹ́rìí sí i ní ti pé ó fún wọn ní ẹ̀mí mímọ́,+ bó ṣe fún àwa náà. 9 Kò sì fi ìyàtọ̀ kankan sáàárín àwa àti àwọn,+ àmọ́ ó wẹ ọkàn wọn mọ́ nípasẹ̀ ìgbàgbọ́.+ 10 Kí ló wá dé tí ẹ fi ń dán Ọlọ́run wò báyìí, tí ẹ̀ ń gbé àjàgà+ tí àwọn baba ńlá wa tàbí àwa fúnra wa kò lè rù kọ́ ọrùn àwọn ọmọ ẹ̀yìn?+ 11 Kàkà bẹ́ẹ̀, a ní ìgbàgbọ́ pé ipasẹ̀ inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Jésù Olúwa+ la fi rí ìgbàlà bíi ti àwọn náà.”+

12 Ni gbogbo wọn bá dákẹ́, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í fetí sílẹ̀ bí Bánábà àti Pọ́ọ̀lù ṣe ń ròyìn ọ̀pọ̀ iṣẹ́ àmì àti iṣẹ́ ìyanu* tí Ọlọ́run ti ṣe nípasẹ̀ wọn láàárín àwọn orílẹ̀-èdè. 13 Lẹ́yìn tí wọ́n parí ọ̀rọ̀ wọn, Jémíìsì fèsì pé: “Ẹ̀yin èèyàn, ẹ̀yin ará, ẹ gbọ́ mi. 14 Símíónì+ ti ròyìn ní kíkún bí Ọlọ́run ṣe yí àfiyèsí rẹ̀ sí àwọn orílẹ̀-èdè fún ìgbà àkọ́kọ́ kí ó lè mú àwọn èèyàn kan jáde fún orúkọ rẹ̀ látinú wọn.+ 15 Ọ̀rọ̀ àwọn Wòlíì sì bá èyí mu, bó ṣe wà lákọsílẹ̀ pé: 16 ‘Lẹ́yìn àwọn nǹkan yìí, màá pa dà, màá sì tún gbé àgọ́* Dáfídì tó ti wó lulẹ̀ dìde; màá tún àwókù rẹ̀ kọ́, màá sì mú kó rí bíi ti tẹ́lẹ̀, 17 kí àwọn tó ṣẹ́ kù lè máa wá Jèhófà* taratara, àwọn àti àwọn èèyàn gbogbo orílẹ̀-èdè, àwọn tí à ń fi orúkọ mi pè, ni Jèhófà* ẹni tó ń ṣe àwọn nǹkan yìí wí,+ 18 àwọn nǹkan tí a ti mọ̀ tipẹ́tipẹ́.’+ 19 Torí náà, ìpinnu* mi ni pé kí a má dààmú àwọn tó ń yíjú sí Ọlọ́run látinú àwọn orílẹ̀-èdè,+ 20 àmọ́ kí a kọ̀wé sí wọn láti ta kété sí àwọn ohun tí àwọn òrìṣà ti sọ di ẹlẹ́gbin,+ sí ìṣekúṣe,*+ sí ohun tí wọ́n fún lọ́rùn pa* àti sí ẹ̀jẹ̀.+ 21 Torí pé láti ìgbà láéláé ni Mósè ti ní àwọn tó ń wàásù nípa rẹ̀ láti ìlú dé ìlú, torí wọ́n ń ka ìwé rẹ̀ sókè nínú àwọn sínágọ́gù ní gbogbo sábáàtì.”+

22 Lẹ́yìn náà, àwọn àpọ́sítélì àti àwọn alàgbà pẹ̀lú gbogbo ìjọ pinnu láti rán àwọn ọkùnrin tí wọ́n yàn láàárín wọn lọ sí Áńtíókù, pẹ̀lú Pọ́ọ̀lù àti Bánábà; wọ́n rán Júdásì tí wọ́n ń pè ní Básábà àti Sílà,+ àwọn tó ń mú ipò iwájú láàárín àwọn ará. 23 Wọ́n kọ̀wé, wọ́n sì fi rán wọn, wọ́n ní:

“Àwọn àpọ́sítélì àti àwọn alàgbà, àwa arákùnrin yín, sí àwọn ará ní Áńtíókù,+ Síríà àti Sìlíṣíà tí wọ́n wá látinú àwọn orílẹ̀-èdè: A kí yín o! 24 Nígbà tí a gbọ́ pé àwọn kan láàárín wa wá sọ́dọ̀ yín, tí wọ́n sì fi ọ̀rọ̀ tí wọ́n sọ kó wàhálà bá yín,+ tí wọ́n fẹ́ dojú yín* dé, bó tiẹ̀ jẹ́ pé a kò fún wọn ní àṣẹ kankan, 25 a ti fìmọ̀ ṣọ̀kan, a sì ti pinnu láti yan àwọn ọkùnrin tí a máa rán sí yín pẹ̀lú àwọn àyànfẹ́ wa, Bánábà àti Pọ́ọ̀lù, 26 àwọn tí wọ́n ti fi ẹ̀mí* wọn lélẹ̀ nítorí orúkọ Olúwa wa Jésù Kristi.+ 27 Nítorí náà, à ń rán Júdásì àti Sílà bọ̀, kí àwọn náà lè fi ọ̀rọ̀ ẹnu jíṣẹ́ + ohun kan náà fún yín. 28 Nítorí ẹ̀mí mímọ́+ àti àwa fúnra wa ti fara mọ́ ọn pé ká má ṣe dì kún ẹrù yín, àyàfi àwọn ohun tó pọn dandan yìí: 29 láti máa ta kété sí àwọn ohun tí wọ́n fi rúbọ sí òrìṣà,+ láti máa ta kété sí ẹ̀jẹ̀,+ sí ohun tí wọ́n fún lọ́rùn pa*+ àti sí ìṣekúṣe.*+ Tí ẹ bá ń yẹra fún àwọn nǹkan yìí délẹ̀délẹ̀, ẹ ó láásìkí. Kí ara yín ó le o!”*

30 Tóò, nígbà tí wọ́n ní kí àwọn ọkùnrin yìí máa lọ, wọ́n lọ sí Áńtíókù, wọ́n kó gbogbo àwọn ọmọ ẹ̀yìn jọ, wọ́n sì fi lẹ́tà náà lé wọn lọ́wọ́. 31 Lẹ́yìn tí wọ́n kà á, ìṣírí tí wọ́n rí gbà mú inú wọn dùn. 32 Júdásì àti Sílà tí àwọn náà jẹ́ wòlíì fi ọ̀pọ̀ àsọyé gba àwọn ará níyànjú, wọ́n sì fún wọn lókun.+ 33 Lẹ́yìn tí wọ́n lo àkókò díẹ̀ níbẹ̀, àwọn ará yọ̀ǹda wọn kí wọ́n máa lọ, wọ́n ní kí wọ́n pa dà sọ́dọ̀ àwọn tó rán wọn wá láyọ̀. 34* —— 35 Àmọ́ Pọ́ọ̀lù àti Bánábà dúró sí Áńtíókù, wọ́n ń kọ́ni, wọ́n sì ń kéde ìhìn rere ọ̀rọ̀ Jèhófà,* àwọn àti ọ̀pọ̀ àwọn míì.

36 Lẹ́yìn ọjọ́ díẹ̀, Pọ́ọ̀lù sọ fún Bánábà pé: “Ní báyìí,* jẹ́ ká pa dà lọ bẹ àwọn ará wò ní gbogbo ìlú tí a ti kéde ọ̀rọ̀ Jèhófà,* ká lè rí bí wọ́n ṣe ń ṣe sí.”+ 37 Bánábà pinnu láti mú Jòhánù tí wọ́n ń pè ní Máàkù dání.+ 38 Àmọ́ Pọ́ọ̀lù ò fara mọ́ ọn pé kí wọ́n mú un dání, ó wò ó pé ó fi àwọn sílẹ̀ ní Panfílíà, kò sì bá wọn lọ sẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù.+ 39 Ni àwọn méjèèjì bá gbaná jẹ, débi pé wọ́n pínyà; Bánábà+ mú Máàkù dání, ó sì wọkọ̀ òkun lọ sí Sápírọ́sì. 40 Pọ́ọ̀lù mú Sílà, ó sì lọ lẹ́yìn tí àwọn ará gbàdúrà pé kí Jèhófà* fi inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí hàn sí i.+ 41 Ó gba Síríà àti Sìlíṣíà kọjá, ó sì ń fún àwọn ìjọ lókun.

16 Nítorí náà, Pọ́ọ̀lù dé Déébè, ó sì dé Lísírà.+ Ọmọ ẹ̀yìn kan wà níbẹ̀ tó ń jẹ́ Tímótì,+ ọmọkùnrin obìnrin Júù kan tó jẹ́ onígbàgbọ́, àmọ́ Gíríìkì ni bàbá rẹ̀, 2 àwọn ará ní Lísírà àti Íkóníónì sì ròyìn rẹ̀ dáadáa. 3 Pọ́ọ̀lù sọ ìfẹ́ ọkàn rẹ̀ pé kí Tímótì tẹ̀ lé òun, ó mú un, ó sì dádọ̀dọ́ rẹ̀* nítorí àwọn Júù tó wà ní agbègbè yẹn,+ torí gbogbo wọn mọ̀ pé Gíríìkì ni bàbá rẹ̀. 4 Bí wọ́n ṣe ń rin ìrìn àjò gba àwọn ìlú náà kọjá, wọ́n ń fi àwọn àṣẹ tí àwọn àpọ́sítélì àti àwọn alàgbà tó wà ní Jerúsálẹ́mù ti pinnu lé lórí jíṣẹ́ fún wọn kí wọ́n lè máa pa wọ́n mọ́.+ 5 Ní tòótọ́, àwọn ìjọ túbọ̀ ń fẹsẹ̀ múlẹ̀ nínú ìgbàgbọ́, wọ́n sì ń pọ̀ sí i lójoojúmọ́.

6 Yàtọ̀ síyẹn, wọ́n rìnrìn àjò gba Fíríjíà àti ilẹ̀ Gálátíà+ kọjá, torí pé ẹ̀mí mímọ́ ò fàyè gbà wọ́n láti sọ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ní ìpínlẹ̀ Éṣíà. 7 Síwájú sí i, nígbà tí wọ́n dé Máísíà, wọ́n sapá láti lọ sí Bítíníà,+ àmọ́ ẹ̀mí Jésù kò gbà wọ́n láyè. 8 Torí náà, wọ́n gba* Máísíà kọjá, wọ́n sì wá sí Tíróásì. 9 Ní òru, Pọ́ọ̀lù rí ìran kan, ọkùnrin ará Makedóníà kan dúró, ó sì ń rọ̀ ọ́ pé: “Sọdá wá sí Makedóníà, kí o sì ràn wá lọ́wọ́.” 10 Gbàrà tí ó ti rí ìran náà, a múra láti lọ sí Makedóníà, torí a gbà pé Ọlọ́run ti pàṣẹ fún wa láti kéde ìhìn rere fún wọn.

11 Torí náà, a wọkọ̀ òkun láti Tíróásì, a sì lọ tààrà sí Sámótírásì, ṣùgbọ́n ní ọjọ́ tó tẹ̀ lé e, a lọ sí Neapólísì; 12 láti ibẹ̀, a lọ sí ìlú Fílípì,+ ìlú tí wọ́n ń ṣàkóso rẹ̀ láti òkèèrè, tó jẹ́ olú ìlú ní agbègbè Makedóníà. A sì lo ọjọ́ díẹ̀ ní ìlú yìí. 13 Ní ọjọ́ Sábáàtì, a lọ sẹ́yìn ẹnubodè létí odò kan, níbi tí a rò pé àwọn èèyàn ti ń gbàdúrà, a jókòó, a sì bẹ̀rẹ̀ sí í bá àwọn obìnrin tí wọ́n pé jọ sọ̀rọ̀. 14 Obìnrin kan tó ń jẹ́ Lìdíà, tó ń ta aṣọ aláwọ̀ pọ́pù, tó wá láti ìlú Tíátírà,+ tó sì jẹ́ olùjọsìn Ọlọ́run, ń fetí sílẹ̀, Jèhófà* sì ṣí ọkàn rẹ̀ sílẹ̀ láti fiyè sí ohun tí Pọ́ọ̀lù ń sọ. 15 Nígbà tí òun àti agbo ilé rẹ̀ ti ṣèrìbọmi,+ ó rọ̀ wá pé: “Tí ẹ bá kà mí sí olóòótọ́ sí Jèhófà,* ẹ wá sí ilé mi kí ẹ sì dúró níbẹ̀.” Ó rí i dájú pé a wá.

16 Ó ṣẹlẹ̀ pé nígbà tí à ń lọ síbi àdúrà, ìránṣẹ́bìnrin kan tó ní ẹ̀mí kan, ẹ̀mí èṣù ìwoṣẹ́,+ pàdé wa. Ó máa ń fi iṣẹ́ wíwò* mú èrè púpọ̀ wá fún àwọn ọ̀gá rẹ̀. 17 Ọmọbìnrin yìí ń tẹ̀ lé Pọ́ọ̀lù àti àwa náà, ó sì ń ké jáde pé: “Ẹrú Ọlọ́run Ẹni Gíga Jù Lọ ni àwọn ọkùnrin yìí,+ wọ́n sì ń kéde ọ̀nà ìgbàlà fún yín.” 18 Ó ṣe èyí fún ọ̀pọ̀ ọjọ́. Níkẹyìn, ó sú Pọ́ọ̀lù, ó yíjú pa dà, ó sì sọ fún ẹ̀mí náà pé: “Mo pàṣẹ fún ọ ní orúkọ Jésù Kristi pé kí o jáde nínú rẹ̀.” Ó sì jáde ní wákàtí yẹn gan-an.+

19 Tóò, nígbà tí àwọn ọ̀gá rẹ̀ rí i pé ọ̀nà ìjẹ wọn ti dí,+ wọ́n gbá Pọ́ọ̀lù àti Sílà mú, wọ́n sì wọ́ wọn lọ sí ibi ọjà lọ́dọ̀ àwọn alákòóso.+ 20 Wọ́n mú wọn dé ọ̀dọ̀ àwọn adájọ́ kéékèèké, wọ́n sọ pé: “Àwọn ọkùnrin yìí ń yọ ìlú wa lẹ́nu gan-an ni.+ Júù ni wọ́n, 21 wọ́n sì ń kéde àwọn àṣà tí kò bófin mu fún wa láti tẹ́wọ́ gbà tàbí láti máa tẹ̀ lé, bẹ́ẹ̀, wọ́n mọ̀ pé ará Róòmù ni wá.” 22 Àwọn èrò tó wà níbẹ̀ dìde sí wọn lẹ́ẹ̀kan náà, lẹ́yìn tí àwọn adájọ́ kéékèèké sì ti ya aṣọ kúrò lára wọn, wọ́n pàṣẹ pé kí wọ́n fi ọ̀pá nà wọ́n.+ 23 Lẹ́yìn tí wọ́n ti lù wọ́n nílùkulù, wọ́n jù wọ́n sẹ́wọ̀n, wọ́n sì pa àṣẹ pé kí ẹni tó ń ṣọ́ àwọn ẹlẹ́wọ̀n máa ṣọ́ wọn lójú méjèèjì.+ 24 Torí pé irú àṣẹ yẹn ni wọ́n pa fún un, ó jù wọ́n sí ẹ̀wọ̀n inú lọ́hùn-ún, ó sì de ẹsẹ̀ wọn mọ́ inú àbà.

25 Àmọ́ láàárín òru, Pọ́ọ̀lù àti Sílà ń gbàdúrà, wọ́n ń fi orin yin Ọlọ́run,+ àwọn ẹlẹ́wọ̀n sì ń fetí sí wọn. 26 Lójijì, ìmìtìtì ilẹ̀ ńlá ṣẹlẹ̀, débi pé àwọn ìpìlẹ̀ ẹ̀wọ̀n mì tìtì. Yàtọ̀ síyẹn, gbogbo ilẹ̀kùn ṣí sílẹ̀ lójú ẹsẹ̀, ìdè gbogbo àwọn tí wọ́n dè sì tú.+ 27 Nígbà tí ẹni tó ń ṣọ́ àwọn ẹlẹ́wọ̀n jí, tó sì rí i pé àwọn ilẹ̀kùn ẹ̀wọ̀n ṣí sílẹ̀, ó fa idà rẹ̀ yọ, ó sì fẹ́ pa ara rẹ̀, ó rò pé àwọn ẹlẹ́wọ̀n ti sá lọ.+ 28 Àmọ́ Pọ́ọ̀lù kígbe sókè pé: “Má ṣe ara rẹ léṣe o, gbogbo wa wà níbí!” 29 Torí náà, ó ní kí wọ́n gbé iná wá, ó sì bẹ́ wọlé, jìnnìjìnnì ti bò ó, ló bá wólẹ̀ níwájú Pọ́ọ̀lù àti Sílà. 30 Ó mú wọn jáde, ó sì sọ pé: “Ẹ̀yin ọ̀gá, kí ni kí n ṣe kí n lè rí ìgbàlà?” 31 Wọ́n sọ pé: “Gba Jésù Olúwa gbọ́, wàá sì rí ìgbàlà, ìwọ àti agbo ilé rẹ.”+ 32 Lẹ́yìn náà, wọ́n sọ ọ̀rọ̀ Jèhófà* fún òun àti gbogbo àwọn tó wà nílé rẹ̀. 33 Ó mú wọn lọ ní òru yẹn, ó sì wẹ ojú ọgbẹ́ wọn. Lẹ́yìn náà, òun àti gbogbo agbo ilé rẹ̀ ṣèrìbọmi láìjáfara.+ 34 Ó mú wọn wá sínú ilé rẹ̀, ó tẹ́ tábìlì síwájú wọn, inú òun àti gbogbo agbo ilé rẹ̀ sì ń dùn gidigidi ní báyìí tí wọ́n ti gba Ọlọ́run gbọ́.

35 Nígbà tí ilẹ̀ mọ́, àwọn adájọ́ kéékèèké rán àwọn akọ́dà lọ láti sọ pé: “Tú àwọn ọkùnrin yẹn sílẹ̀.” 36 Ẹni tó ń ṣọ́ àwọn ẹlẹ́wọ̀n ròyìn ohun tí wọ́n sọ fún Pọ́ọ̀lù, pé: “Àwọn adájọ́ kéékèèké ti rán àwọn èèyàn wá pé kí á tú ẹ̀yin méjèèjì sílẹ̀. Torí náà, ẹ jáde ní báyìí, kí ẹ sì máa lọ ní àlàáfíà.” 37 Àmọ́ Pọ́ọ̀lù sọ fún wọn pé: “Wọ́n nà wá lẹ́gba ní gbangba láìdá wa lẹ́bi,* bó tiẹ̀ jẹ́ pé ará Róòmù ni wá,+ wọ́n jù wá sẹ́wọ̀n. Ṣé wọ́n wá fẹ́ tì wá jáde ní bòókẹ́lẹ́ ni? Rárá o! Kí àwọn fúnra wọn wá mú wa jáde.” 38 Àwọn akọ́dà ròyìn ohun tí wọ́n sọ fún àwọn adájọ́ kéékèèké. Ẹ̀rù bà wọ́n nígbà tí wọ́n gbọ́ pé ará Róòmù+ ni àwọn ọkùnrin náà. 39 Torí náà, wọ́n wá, wọ́n bẹ̀ wọ́n, lẹ́yìn tí wọ́n sì mú wọn jáde, wọ́n rọ̀ wọ́n pé kí wọ́n kúrò ní ìlú náà. 40 Àmọ́ wọ́n jáde kúrò ní ẹ̀wọ̀n, wọ́n sì lọ sí ilé Lìdíà; nígbà tí wọ́n rí àwọn ará, wọ́n fún wọn ní ìṣírí,+ wọ́n sì lọ.

17 Wọ́n rin ìrìn àjò gba Áńfípólì àti Apolóníà kọjá, wọ́n sì wá sí Tẹsalóníkà,+ níbi tí sínágọ́gù àwọn Júù wà. 2 Torí náà, bí àṣà Pọ́ọ̀lù,+ ó wọlé lọ bá wọn, ó sì bá wọn fèròwérò látinú Ìwé Mímọ́ fún sábáàtì mẹ́ta,+ 3 ó ń ṣàlàyé, ó sì ń tọ́ka sí àwọn ohun tó fi ẹ̀rí hàn pé ó pọn dandan kí Kristi jìyà,+ kí ó sì dìde kúrò nínú ikú,+ ó sọ pé: “Èyí ni Kristi náà, Jésù tí mò ń kéde fún yín.” 4 Nítorí èyí, àwọn kan lára wọn di onígbàgbọ́, wọ́n sì dara pọ̀ mọ́ Pọ́ọ̀lù àti Sílà,+ ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn Gíríìkì tó ń sin Ọlọ́run àti díẹ̀ lára àwọn obìnrin sàràkí-sàràkí ṣe bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú.

5 Àmọ́ inú bí àwọn Júù,+ wọ́n kó àwọn ọkùnrin burúkú kan jọ tí wọ́n jẹ́ aláìríkan-ṣèkan ní ibi ọjà, wọ́n di àwùjọ onírúgúdù, wọ́n sì dá ìdàrúdàpọ̀ sílẹ̀ nínú ìlú náà. Wọ́n ya wọ ilé Jásónì, wọ́n ń wá ọ̀nà láti mú Pọ́ọ̀lù àti Sílà wá fún àwùjọ náà. 6 Nígbà tí wọn ò rí wọn, wọ́n wọ́ Jásónì àti àwọn arákùnrin kan lọ sọ́dọ̀ àwọn alákòóso ìlú, wọ́n ń pariwo pé: “Àwọn ọkùnrin tó ń dojú ilẹ̀ ayé tí à ń gbé dé* ti wá síbí o,+ 7 Jásónì sì gbà wọ́n lálejò. Gbogbo àwọn ọkùnrin yìí ló ń ta ko àwọn àṣẹ Késárì, tí wọ́n ń sọ pé ọba míì wà tó ń jẹ́ Jésù.”+ 8 Nígbà tí àwọn èrò àti àwọn alákòóso ìlú gbọ́ ọ̀rọ̀ yìí, ẹ̀rù bà wọ́n; 9 lẹ́yìn tí wọ́n gba ohun ìdúró tí ó tó* lọ́wọ́ Jásónì àti àwọn yòókù, wọ́n fi wọ́n sílẹ̀.

10 Gbàrà tí ilẹ̀ ṣú, àwọn ará ní kí Pọ́ọ̀lù àti Sílà lọ sí Bèróà. Nígbà tí wọ́n dé ibẹ̀, wọ́n wọ sínágọ́gù àwọn Júù. 11 Àwọn tó wà ní Bèróà ní ọkàn rere ju àwọn tó wà ní Tẹsalóníkà lọ, torí pé wọ́n gba ọ̀rọ̀ náà tọkàntọkàn wọ́n sì ń ṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ kínníkínní lójoojúmọ́ láti rí i bóyá àwọn nǹkan yìí rí bẹ́ẹ̀. 12 Nítorí náà, ọ̀pọ̀ lára wọn di onígbàgbọ́, bẹ́ẹ̀ sì ni díẹ̀ lára àwọn obìnrin Gíríìkì tó ní orúkọ rere àti lára àwọn ọkùnrin wọn. 13 Àmọ́ nígbà tí àwọn Júù ní Tẹsalóníkà gbọ́ pé Pọ́ọ̀lù ti ń kéde ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ní Bèróà, wọ́n wá síbẹ̀ láti ru àwọn èèyàn sókè, kí wọ́n sì kó sí wọn nínú.+ 14 Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, àwọn ará ní kí Pọ́ọ̀lù máa lọ sí etí òkun,+ àmọ́ Sílà àti Tímótì dúró síbẹ̀. 15 Nígbà tí àwọn tó wà pẹ̀lú Pọ́ọ̀lù mú un dé Áténì, wọ́n pa dà lẹ́yìn tí Pọ́ọ̀lù sọ fún wọn pé kí Sílà àti Tímótì+ tètè wá bá òun ní kíá.

16 Bí Pọ́ọ̀lù ṣe ń dúró dè wọ́n ní Áténì, inú bí i nígbà tó rí i pé àwọn òrìṣà kún inú ìlú náà. 17 Torí náà, ó bẹ̀rẹ̀ sí í bá àwọn Júù àti àwọn míì tó ń jọ́sìn Ọlọ́run fèròwérò nínú sínágọ́gù, ó sì ń ṣe bẹ́ẹ̀ lójoojúmọ́ ní ibi ọjà pẹ̀lú àwọn tó bá wà ní àrọ́wọ́tó. 18 Àmọ́ lára àwọn onímọ̀ ọgbọ́n orí Epikúríà àti ti Sítọ́ìkì bẹ̀rẹ̀ sí í bá a jiyàn, àwọn kan ń sọ pé: “Kí ni onírèégbè yìí fẹ́ sọ?” Àwọn míì ń sọ pé: “Ó jọ ẹni tó ń kéde àwọn ọlọ́run àjèjì.” Èyí jẹ́ nítorí pé ó ń kéde ìhìn rere Jésù àti àjíǹde.+ 19 Nítorí náà, wọ́n gbá a mú, wọ́n sì mú un lọ sí Áréópágù, wọ́n sọ pé: “Ǹjẹ́ a lè mọ ohun tí ẹ̀kọ́ tuntun tí ò ń sọ yìí jẹ́? 20 Nítorí àwọn ohun tó ṣàjèjì sí etí wa lò ń sọ, a sì fẹ́ mọ ohun tí wọ́n túmọ̀ sí.” 21 Ní tòótọ́, gbogbo àwọn ará Áténì àti àwọn àjèjì tó ń gbé níbẹ̀* kò ní nǹkan míì tí wọ́n ń fi àkókò tí ọwọ́ wọn bá dilẹ̀ ṣe ju pé kí wọ́n máa sọ̀rọ̀ tàbí kí wọ́n máa fetí sí ohun tuntun. 22 Ni Pọ́ọ̀lù bá dúró láàárín Áréópágù,+ ó sì sọ pé:

“Ẹ̀yin èèyàn Áténì, mo kíyè sí pé nínú ohun gbogbo, ó jọ pé ẹ bẹ̀rù àwọn ọlọ́run ju bí àwọn yòókù ṣe bẹ̀rù wọn lọ.*+ 23 Bí àpẹẹrẹ, bí mo ṣe ń lọ, tí mo sì ń fara balẹ̀ wo àwọn ohun tí ẹ̀ ń júbà,* mo rí pẹpẹ kan, tí wọ́n kọ àkọlé sí pé ‘Sí Ọlọ́run Àìmọ̀.’ Nítorí náà, ohun tí ẹ̀ ń sìn láìmọ̀ ni mo wá kéde fún yín. 24 Ọlọ́run tó dá ayé àti gbogbo ohun tó wà nínú rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí òun fúnra rẹ̀ ṣe jẹ́ Olúwa ọ̀run àti ayé,+ kì í gbé inú àwọn tẹ́ńpìlì tí a fi ọwọ́ kọ́;+ 25 bẹ́ẹ̀ ni kì í retí pé kí èèyàn ran òun lọ́wọ́ bíi pé ó nílò ohunkóhun,+ nítorí òun fúnra rẹ̀ ló ń fún gbogbo èèyàn ní ìyè àti èémí+ àti ohun gbogbo. 26 Láti ara ọkùnrin kan ló ti dá+ àwọn èèyàn gbogbo orílẹ̀-èdè láti máa gbé lórí gbogbo ilẹ̀ ayé,+ ó yan àkókò fún àwọn nǹkan, ó sì pa ààlà ibi tí àwọn èèyàn á máa gbé,+ 27 kí wọ́n lè máa wá Ọlọ́run, tí wọ́n bá lè táràrà fún un, kí wọ́n sì rí i ní ti gidi,+ bó tilẹ̀ jẹ́ pé, ní tòótọ́, kò jìnnà sí ẹnì kọ̀ọ̀kan wa. 28 Torí ipasẹ̀ rẹ̀ ni a fi ní ìyè, tí à ń rìn, tí a sì wà, àní gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ àwọn kan lára àwọn akéwì yín tó sọ pé, ‘Nítorí àwa náà jẹ́ ọmọ* rẹ̀.’

29 “Nítorí náà, bí a ṣe jẹ́ ọmọ* Ọlọ́run,+ kò yẹ kí a rò pé Olú Ọ̀run rí bíi wúrà tàbí fàdákà tàbí òkúta, bí ohun tí a fi ọgbọ́n àti iṣẹ́ ọnà èèyàn gbẹ́ lére.+ 30 Lóòótọ́, Ọlọ́run ti gbójú fo ìgbà àìmọ̀ yìí;+ àmọ́ ní báyìí, ó ń sọ fún gbogbo èèyàn níbi gbogbo pé kí wọ́n ronú pìwà dà. 31 Torí ó ti dá ọjọ́ kan tó máa fi òdodo ṣèdájọ́ + ayé láti ọwọ́ ọkùnrin kan tó ti yàn, ó sì ti pèsè ẹ̀rí tó dájú fún gbogbo èèyàn bó ṣe jí i dìde kúrò nínú ikú.”+

32 Nígbà tí wọ́n gbọ́ nípa àjíǹde àwọn òkú, àwọn kan bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe yẹ̀yẹ́,+ àwọn míì sì sọ pé: “A máa gbọ́ ọ̀rọ̀ yìí lẹ́nu rẹ nígbà míì.” 33 Torí náà, Pọ́ọ̀lù fi wọ́n sílẹ̀, 34 àmọ́ àwọn kan dara pọ̀ mọ́ ọn, wọ́n sì di onígbàgbọ́. Lára wọn ni Díónísíù tó jẹ́ adájọ́ ní kọ́ọ̀tù Áréópágù àti obìnrin kan tó ń jẹ́ Dámárì pẹ̀lú àwọn míì.

18 Lẹ́yìn èyí, ó kúrò ní Áténì, ó sì wá sí Kọ́ríńtì. 2 Ó rí Júù kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Ákúílà,+ ọmọ ìbílẹ̀ Pọ́ńtù, tí kò tíì pẹ́ tí òun àti Pírísílà ìyàwó rẹ̀ dé láti Ítálì, torí Kíláúdíù ti pàṣẹ pé kí àwọn Júù kúrò ní Róòmù. Nítorí náà, ó lọ bá wọn, 3 torí pé iṣẹ́ kan náà ni wọ́n jọ ń ṣe, ó dúró sí ilé wọn, ó sì ń bá wọn ṣiṣẹ́,+ torí iṣẹ́ àgọ́ pípa ni wọ́n ń ṣe. 4 Ó máa ń sọ àsọyé* nínú sínágọ́gù+ ní gbogbo sábáàtì,+ ó sì máa ń yí àwọn Júù àti Gíríìkì lérò pa dà.

5 Nígbà tí Sílà+ àti Tímótì+ wá láti Makedóníà, ọ̀rọ̀ Ọlọ́run mú kí ọwọ́ Pọ́ọ̀lù dí gan-an, ó ń jẹ́rìí fún àwọn Júù láti fi ẹ̀rí hàn pé Jésù ni Kristi náà.+ 6 Àmọ́ nígbà tí wọn ò yéé ṣàtakò sí i, tí wọ́n sì ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ láìdáa, ó gbọn ẹ̀wù rẹ̀,+ ó sì sọ fún wọn pé: “Kí ẹ̀jẹ̀ yín wà lórí ẹ̀yin fúnra yín.+ Ọrùn mi mọ́.+ Láti ìsinsìnyí lọ, màá lọ máa bá àwọn èèyàn orílẹ̀-èdè.”+ 7 Torí náà, ó kúrò níbẹ̀,* ó sì lọ sí ilé ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Títíọ́sì Jọ́sítù, olùjọ́sìn Ọlọ́run, tí ilé rẹ̀ wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ sínágọ́gù. 8 Àmọ́ Kírípọ́sì,+ alága sínágọ́gù, di onígbàgbọ́ nínú Olúwa, òun pẹ̀lú gbogbo agbo ilé rẹ̀. Ọ̀pọ̀ àwọn ará Kọ́ríńtì tí wọ́n gbọ́ bẹ̀rẹ̀ sí í gbà gbọ́, wọ́n sì ṣèrìbọmi. 9 Síwájú sí i, Olúwa sọ fún Pọ́ọ̀lù ní òru nínú ìran pé: “Má bẹ̀rù, máa sọ̀rọ̀ nìṣó, má sì dákẹ́, 10 torí mo wà pẹ̀lú rẹ,+ ẹnikẹ́ni ò ní kọ lù ọ́ láti ṣe ọ́ léṣe; nítorí mo ní ọ̀pọ̀ èèyàn ní ìlú yìí.” 11 Torí náà, ó lo ọdún kan àti oṣù mẹ́fà níbẹ̀, ó ń kọ́ni ní ọ̀rọ̀ Ọlọ́run láàárín wọn.

12 Lásìkò tí Gálíò jẹ́ alákòóso ìbílẹ̀* Ákáyà, àwọn Júù gbìmọ̀ pọ̀, wọ́n dìde sí Pọ́ọ̀lù, wọ́n sì mú un lọ síwájú ìjókòó ìdájọ́, 13 wọ́n sọ pé: “Ọkùnrin yìí ń yí àwọn èèyàn lérò pa dà láti máa sin Ọlọ́run lọ́nà tó ta ko òfin.” 14 Àmọ́ bí Pọ́ọ̀lù ṣe fẹ́ bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀, Gálíò sọ fún àwọn Júù pé: “Ẹ̀yin Júù, tó bá jẹ́ lórí ìwà àìtọ́ tàbí ìwà ọ̀daràn ni, ó máa bọ́gbọ́n mu pé kí n fi sùúrù gbọ́ yín. 15 Ṣùgbọ́n tó bá jẹ́ àríyànjiyàn lórí ọ̀rọ̀ àti àwọn orúkọ àti òfin yín ni,+ ẹ̀yin fúnra yín ni kí ẹ lọ bójú tó o. Mi ò fẹ́ ṣe ìdájọ́ lórí àwọn nǹkan yìí.” 16 Ló bá lé wọn kúrò níbi ìjókòó ìdájọ́. 17 Nítorí náà, gbogbo wọn gbá Sótínésì,+ alága sínágọ́gù mú, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í lù ú níwájú ìjókòó ìdájọ́. Àmọ́ Gálíò kò dá sí ohun tó ń ṣẹlẹ̀ rárá.

18 Lẹ́yìn tí Pọ́ọ̀lù lo ọjọ́ mélòó kan sí i níbẹ̀, ó dágbére fún àwọn ará, ó wọkọ̀ òkun lọ sí Síríà, Pírísílà àti Ákúílà sì bá a lọ. Ó gé irun orí rẹ̀ mọ́lẹ̀ ní Kẹnkíríà,+ torí ó ti jẹ́ ẹ̀jẹ́ kan. 19 Nígbà tí wọ́n dé Éfésù, ó fi wọ́n sílẹ̀ níbẹ̀; àmọ́ ó wọ sínágọ́gù, ó sì ń bá àwọn Júù fèròwérò.+ 20 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ń sọ fún un pé kó dúró sí i lọ́dọ̀ àwọn, kò gbà, 21 àmọ́ ó dágbére, ó sì sọ fún wọn pé: “Màá tún pa dà sọ́dọ̀ yín, tí Jèhófà* bá fẹ́.” Ó wá wọkọ̀ òkun láti Éfésù, 22 ó sì wá sí Kesaríà. Ó jáde lọ,* ó sì kí ìjọ, lẹ́yìn náà ó lọ sí Áńtíókù.+

23 Lẹ́yìn tó lo àkókò díẹ̀ níbẹ̀, ó kúrò, ó sì ń lọ láti ibì kan sí ibòmíì ní ilẹ̀ Gálátíà àti Fíríjíà,+ ó ń fún gbogbo ọmọ ẹ̀yìn lókun.+

24 Júù kan wà tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Àpólò,+ ọmọ ìbílẹ̀ Alẹkisáńdíríà, ó dé sí Éfésù; ọkùnrin sọ̀rọ̀sọ̀rọ̀ tó mọ Ìwé Mímọ́ dunjú ni. 25 Ọkùnrin yìí ti gba ẹ̀kọ́* nípa ọ̀nà Jèhófà,* iná ẹ̀mí sì ń jó nínú rẹ̀, ó ń sọ̀rọ̀, ó sì ń kọ́ni ní àwọn nǹkan tó jẹ mọ́ Jésù lọ́nà tó péye, àmọ́ ìrìbọmi Jòhánù nìkan ló mọ̀. 26 Ó bẹ̀rẹ̀ sí í fìgboyà sọ̀rọ̀ nínú sínágọ́gù, nígbà tí Pírísílà àti Ákúílà+ gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀, wọ́n mú un wọ àwùjọ wọn, wọ́n sì ṣàlàyé ọ̀nà Ọlọ́run fún un lọ́nà tó túbọ̀ péye. 27 Bákan náà, torí pé ó fẹ́ kọjá sí Ákáyà, àwọn ará kọ̀wé sí àwọn ọmọ ẹ̀yìn, wọ́n rọ̀ wọ́n pé kí wọ́n gbà á tọwọ́tẹsẹ̀. Torí náà, nígbà tó débẹ̀, ó ṣèrànwọ́ púpọ̀ fún àwọn tó ti di onígbàgbọ́ nípasẹ̀ inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Ọlọ́run; 28 ó ń sọ̀rọ̀ ní gbangba pẹ̀lú ìtara, bó ṣe ń fi ẹ̀rí hàn kedere pé àwọn Júù kò tọ̀nà, tó sì ń fi hàn nínú Ìwé Mímọ́ pé Jésù ni Kristi náà.+

19 Bọ́jọ́ ṣe ń gorí ọjọ́, Àpólò+ wà ní Kọ́ríńtì, Pọ́ọ̀lù gba àwọn agbègbè tó jìnnà sí òkun kọjá, ó sì wá sí Éfésù.+ Ó rí àwọn ọmọ ẹ̀yìn kan níbẹ̀, 2 ó sì béèrè lọ́wọ́ wọn pé: “Ṣé ẹ gba ẹ̀mí mímọ́ nígbà tí ẹ di onígbàgbọ́?”+ Wọ́n dá a lóhùn pé: “Hàà, a kò gbọ́ ọ rí pé ẹ̀mí mímọ́ wà.” 3 Ó wá sọ pé: “Irú ìrìbọmi wo lẹ wá ṣe?” Wọ́n sọ pé: “Ìrìbọmi Jòhánù ni.”+ 4 Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Ìrìbọmi tí Jòhánù ṣe fún àwọn èèyàn jẹ́ àmì ìrònúpìwàdà,+ ó ń sọ fún wọn pé kí wọ́n gba ẹni tó ń bọ̀ lẹ́yìn òun gbọ́,+ ìyẹn Jésù.” 5 Bí wọ́n ṣe gbọ́ ọ̀rọ̀ yìí, a batisí wọn ní orúkọ Jésù Olúwa. 6 Nígbà tí Pọ́ọ̀lù gbé ọwọ́ lé wọn, ẹ̀mí mímọ́ bà lé wọn,+ wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í sọ èdè àjèjì, wọ́n sì ń sọ tẹ́lẹ̀.+ 7 Lápapọ̀, wọ́n jẹ́ nǹkan bí ọkùnrin méjìlá (12).

8 Fún oṣù mẹ́ta, ó ń wọ sínágọ́gù,+ ó sì ń fìgboyà sọ̀rọ̀, ó ń sọ àsọyé, ó sì ń bá wọn fèròwérò nípa Ìjọba Ọlọ́run lọ́nà tó ń yíni lérò pa dà.+ 9 Àmọ́ nígbà tí àwọn kan kọ̀ jálẹ̀ pé àwọn ò ní gbà á gbọ́,* tí wọ́n sì ń sọ̀rọ̀ burúkú nípa Ọ̀nà Náà+ lójú ọ̀pọ̀ èèyàn, ó kúrò lọ́dọ̀ wọn,+ ó sì ya àwọn ọmọ ẹ̀yìn sọ́tọ̀ kúrò lára wọn, ó ń sọ àsọyé lójoojúmọ́ nínú gbọ̀ngàn àpéjọ ilé ẹ̀kọ́ Tíránù. 10 Èyí ń bá a lọ fún ọdún méjì, tí gbogbo àwọn tó ń gbé ní ìpínlẹ̀ Éṣíà fi gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa, àti Júù àti Gíríìkì.

11 Ọlọ́run ń ṣe àwọn iṣẹ́ agbára tó ṣàrà ọ̀tọ̀ láti ọwọ́ Pọ́ọ̀lù nìṣó,+ 12 débi pé, àwọn aṣọ àti épírọ́ọ̀nù* tó kan ara rẹ̀ pàápàá ni wọ́n ń mú lọ bá àwọn tó ń ṣàìsàn,+ àwọn àìsàn náà ń fi wọ́n sílẹ̀, àwọn ẹ̀mí burúkú sì ń jáde kúrò lára wọn.+ 13 Àmọ́ lára àwọn Júù tó ń rìnrìn àjò kiri, tí wọ́n ń lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde náà gbìyànjú láti máa pe orúkọ Jésù Olúwa sórí àwọn tó ní àwọn ẹ̀mí burúkú; wọ́n á ní: “Mo pàṣẹ tó rinlẹ̀ fún yín nípasẹ̀ Jésù tí Pọ́ọ̀lù ń wàásù rẹ̀.”+ 14 Lásìkò yìí, àwọn ọmọkùnrin méje kan wà tí wọ́n ń ṣe èyí, wọ́n jẹ́ ọmọ Síkéfà, ọ̀kan lára àwọn olórí àlùfáà àwọn Júù. 15 Àmọ́ ẹ̀mí burúkú náà dá wọn lóhùn pé: “Mo mọ Jésù,+ mo sì mọ Pọ́ọ̀lù;+ àmọ́ ta lẹ̀yin?” 16 Ni ọkùnrin tó ní ẹ̀mí burúkú náà bá bẹ́ mọ́ wọn, ó mú wọn balẹ̀ lọ́kọ̀ọ̀kan, ó sì borí wọn, débi pé ìhòòhò ni wọ́n sá jáde nínú ilé náà, tí ara wọn sì gbọgbẹ́. 17 Ọ̀rọ̀ yìí dé etí gbogbo èèyàn, ó dé etí àwọn Júù àti àwọn Gíríìkì tó ń gbé ní Éfésù; ẹ̀rù ba gbogbo wọn, àwọn èèyàn sì ń gbé orúkọ Jésù Olúwa ga. 18 Ọ̀pọ̀ lára àwọn tó ti di onígbàgbọ́ sì ń jáde wá jẹ́wọ́, wọ́n ń sọ àwọn ohun tí wọ́n ti ṣe tẹ́lẹ̀ ní gbangba. 19 Ní tòótọ́, ọ̀pọ̀ lára àwọn tó ń pidán kó àwọn ìwé wọn jọ, wọ́n sì dáná sun wọ́n níwájú gbogbo èèyàn.+ Wọ́n ṣírò iye tó jẹ́, wọ́n sì rí i pé ó tó ẹgbẹ̀rún lọ́nà àádọ́ta (50,000) ẹyọ fàdákà. 20 Nípa bẹ́ẹ̀, ọ̀rọ̀ Jèhófà* ń gbilẹ̀ nìṣó, ó sì ń borí lọ́nà tó lágbára.+

21 Lẹ́yìn tí àwọn nǹkan yìí ti ṣẹlẹ̀, Pọ́ọ̀lù pinnu lọ́kàn rẹ̀ pé, lẹ́yìn tí òun bá ti la Makedóníà+ àti Ákáyà kọjá, òun á rìnrìn àjò lọ sí Jerúsálẹ́mù.+ Ó sọ pé: “Lẹ́yìn tí mo bá lọ síbẹ̀, mo gbọ́dọ̀ dé Róòmù pẹ̀lú.”+ 22 Torí náà, ó rán Tímótì+ àti Érásítù,+ méjì lára àwọn tó ń ṣe ìránṣẹ́ fún un, lọ sí Makedóníà, àmọ́ òun fúnra rẹ̀ lo àkókò díẹ̀ sí i ní ìpínlẹ̀ Éṣíà.

23 Ní àkókò yẹn, àwọn èèyàn dá rògbòdìyàn+ púpọ̀ sílẹ̀ nípa Ọ̀nà Náà.+ 24 Nítorí ọkùnrin kan wà tó ń jẹ́ Dímẹ́tíríù, alágbẹ̀dẹ fàdákà tó ń fi fàdákà ṣe ojúbọ Átẹ́mísì, ó máa ń mú èrè púpọ̀ wọlé fún àwọn oníṣẹ́ ọnà.+ 25 Ó kó wọn jọ pẹ̀lú àwọn míì tó ń ṣe irú àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀, ó sì sọ pé: “Ẹ̀yin èèyàn, ẹ mọ̀ dáadáa pé òwò yìí ló mú ká láásìkí. 26 Ní báyìí, ẹ ti rí i, ẹ sì ti gbọ́ bí Pọ́ọ̀lù yìí ṣe yí ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn lérò pa dà, tó sì mú kí wọ́n ní èrò míì, kì í ṣe ní Éfésù nìkan,+ àmọ́ ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ ní gbogbo ìpínlẹ̀ Éṣíà, tó ń sọ pé àwọn ọlọ́run tí a fi ọwọ́ ṣe kì í ṣe ọlọ́run.+ 27 Yàtọ̀ síyẹn, ewu tó wà níbẹ̀ kọjá pé àwọn èèyàn á máa bẹnu àtẹ́ lu òwò wa, wọn ò tún ní ka tẹ́ńpìlì abo ọlọ́run ńlá tó ń jẹ́ Átẹ́mísì sí, ẹni tí gbogbo ìpínlẹ̀ Éṣíà àti ilẹ̀ ayé tí à ń gbé ń jọ́sìn kò sì ní níyì mọ́.” 28 Bí àwọn èèyàn náà ṣe gbọ́ ọ̀rọ̀ yìí, wọ́n gbaná jẹ, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í pariwo pé: “Títóbi ni Átẹ́mísì àwọn ará Éfésù!”

29 Ni gbogbo ìlú bá dà rú, wọ́n sì jọ rọ́ wọnú gbọ̀ngàn ìwòran náà, wọ́n wọ́ Gáyọ́sì àti Àrísítákọ́sì jáde,+ àwọn ará Makedóníà tí wọ́n máa ń bá Pọ́ọ̀lù rìnrìn àjò. 30 Ní ti Pọ́ọ̀lù, ó fẹ́ wọlé lọ bá àwọn èèyàn náà, àmọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn kò gbà á láyè. 31 Kódà, lára àwọn kọmíṣọ́nnà àjọyọ̀ àti eré tí wọ́n fẹ́ràn rẹ̀ ránṣẹ́ sí i, wọ́n rọ̀ ọ́ pé kí ó má fi ẹ̀mí rẹ̀ wewu pé òun fẹ́ wọnú gbọ̀ngàn ìwòran náà. 32 Nítorí àpéjọ náà ti dà rú, bí àwọn kan ṣe ń pariwo tibí ni àwọn míì ń pariwo tọ̀hún, ọ̀pọ̀ nínú wọn ni ò sì mọ ìdí tí wọ́n fi kóra jọ. 33 Nítorí náà, wọ́n mú Alẹkisáńdà jáde láàárín èrò, àwọn Júù tì í síwájú, Alẹkisáńdà sì ju ọwọ́ rẹ̀, ó fẹ́ sọ̀rọ̀ láti gbèjà ara rẹ̀ níwájú àwọn èèyàn náà. 34 Àmọ́ nígbà tí wọ́n rí i pé Júù ni, gbogbo wọn pa ohùn pọ̀, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í kígbe fún nǹkan bíi wákàtí méjì pé: “Títóbi ni Átẹ́mísì àwọn ará Éfésù!”

35 Nígbà tí akọ̀wé ìlú náà wá mú kí ọ̀pọ̀ èèyàn náà dákẹ́, ó sọ pé: “Ẹ̀yin èèyàn Éfésù, ta ni nínú gbogbo èèyàn ni kò mọ̀ pé ìlú àwọn ará Éfésù ni ìlú tó ń bójú tó tẹ́ńpìlì Átẹ́mísì ńlá àti ère tó já bọ́ láti ọ̀run? 36 Nígbà tí ẹnikẹ́ni ò ti lè sọ pé àwọn nǹkan yìí ò rí bẹ́ẹ̀, ó yẹ kí ẹ fara balẹ̀, kí ẹ má sì fi wàdùwàdù ṣe nǹkan. 37 Nítorí àwọn ọkùnrin tí ẹ mú wá síbí yìí kò jí nǹkan ní tẹ́ńpìlì, bẹ́ẹ̀ ni wọn ò sọ̀rọ̀ òdì sí abo ọlọ́run wa. 38 Torí náà, tí Dímẹ́tíríù+ àti àwọn oníṣẹ́ ọnà tó wà pẹ̀lú rẹ̀ bá ní ẹjọ́ pẹ̀lú ẹnì kan, àwọn ọjọ́ kọ́ọ̀tù wà, àwọn alákòóso ìbílẹ̀* sì wà; kí wọ́n wá fẹ̀sùn kan ara wọn. 39 Àmọ́ tó bá jẹ́ pé ohun tó ju èyí lọ lẹ̀ ń wá, inú àpéjọ tó bófin mu ni wọ́n ti máa ṣèpinnu lórí rẹ̀. 40 Ohun tó ṣẹlẹ̀ lónìí lè mú kí wọ́n fẹ̀sùn kàn wá pé à ń dìtẹ̀ sí ìjọba, torí kò sí ìdí kankan tí a lè sọ pé ó fà á tí àwùjọ onírúgúdù yìí fi kóra jọ.” 41 Lẹ́yìn tó sọ ọ̀rọ̀ yìí, ó tú àpéjọ náà ká.

20 Nígbà tí rúkèrúdò náà rọlẹ̀, Pọ́ọ̀lù ránṣẹ́ pe àwọn ọmọ ẹ̀yìn, lẹ́yìn tó fún wọn ní ìṣírí, tó sì dágbére fún wọn, ó bẹ̀rẹ̀ ìrìn àjò rẹ̀ lọ sí Makedóníà. 2 Lẹ́yìn tó gba àwọn agbègbè náà kọjá, tó sì ń fún àwọn tó wà níbẹ̀ ní ọ̀pọ̀ ìṣírí, ó dé ilẹ̀ Gíríìsì. 3 Ó lo oṣù mẹ́ta níbẹ̀, àmọ́ torí pé àwọn Júù+ gbìmọ̀ pọ̀ láti pa á nígbà tó fẹ́ wọkọ̀ lọ sí Síríà, ó pinnu pé òun á gba Makedóníà pa dà. 4 Àwọn tó bá a lọ ni Sópátérì ọmọ Párù ará Bèróà, Àrísítákọ́sì+ àti Sẹ́kúńdù láti Tẹsalóníkà, Gáyọ́sì ará Déébè, Tímótì+ pẹ̀lú Tíkíkù+ àti Tírófímù+ láti ìpínlẹ̀ Éṣíà. 5 Àwọn ọkùnrin yìí lọ ṣáájú wa, wọ́n sì dúró dè wá ní Tíróásì; 6 àmọ́ a wọkọ̀ òkun láti ìlú Fílípì lẹ́yìn àjọyọ̀ Búrẹ́dì Aláìwú,+ láàárín ọjọ́ márùn-ún, a dé ọ̀dọ̀ wọn ní Tíróásì, a sì lo ọjọ́ méje níbẹ̀.

7 Ní ọjọ́ kìíní ọ̀sẹ̀, nígbà tí a kóra jọ láti jẹun, Pọ́ọ̀lù bẹ̀rẹ̀ sí í bá wọn sọ̀rọ̀, torí pé ọjọ́ kejì ló máa kúrò níbẹ̀; ó sì sọ̀rọ̀ títí di ọ̀gànjọ́ òru. 8 Àwọn fìtílà mélòó kan wà ní yàrá òkè tí a kóra jọ sí. 9 Ọ̀dọ́kùnrin kan tó ń jẹ́ Yútíkọ́sì jókòó sójú fèrèsé,* ó sùn lọ fọnfọn nígbà tí Pọ́ọ̀lù ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ, oorun ti gbé e lọ, ló bá ṣubú láti àjà kẹta, ó sì ti kú nígbà tí wọ́n fi máa gbé e. 10 Àmọ́ Pọ́ọ̀lù lọ sísàlẹ̀, ó dùbúlẹ̀ lé e, ó sì gbá a mọ́ra,+ ó sọ pé: “Ẹ dákẹ́ ariwo, torí ó ti jí.”*+ 11 Lẹ́yìn náà, ó gòkè pẹ̀tẹ́ẹ̀sì lọ, ó bẹ̀rẹ̀ oúnjẹ,* ó sì ń jẹun. Ó ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ títí ilẹ̀ fi mọ́, lẹ́yìn náà, ó kúrò níbẹ̀. 12 Torí náà, wọ́n mú ọmọkùnrin náà lọ láàyè, ìtùnú tí wọ́n rí gbà sì kọjá sísọ.

13 A wá tẹ̀ síwájú lọ sídìí ọkọ̀ òkun, a sì wọkọ̀ lọ sí Ásò, níbi tí a ní i lọ́kàn pé a ti máa fi ọkọ̀ gbé Pọ́ọ̀lù, torí lẹ́yìn tó ti sọ ohun tí a máa ṣe lórí ọ̀rọ̀ yìí, òun fúnra rẹ̀ ní i lọ́kàn láti fi ẹsẹ̀ rìn lọ síbẹ̀. 14 Torí náà, nígbà tó bá wa ní Ásò, a fi ọkọ̀ gbé e, a sì lọ sí Mítílénè. 15 Lọ́jọ́ tó tẹ̀ lé e, a wọkọ̀ kúrò níbẹ̀, a dé òdìkejì Kíósì, àmọ́ ní ọjọ́ kejì, a fẹsẹ̀ kan dé Sámósì, a sì dé Mílétù ní ọjọ́ tó tẹ̀ lé e. 16 Pọ́ọ̀lù ti pinnu láti wọkọ̀ òkun kọjá Éfésù,+ kó má bàa lo àkókò kankan ní ìpínlẹ̀ Éṣíà, torí ó fẹ́ tètè dé Jerúsálẹ́mù+ ní ọjọ́ Àjọyọ̀ Pẹ́ńtíkọ́sì, bí ó bá ṣeé ṣe fún un.

17 Àmọ́ láti Mílétù, ó ránṣẹ́ sí Éfésù, ó ní kí wọ́n pe àwọn alàgbà ìjọ wá. 18 Nígbà tí wọ́n dé ọ̀dọ̀ rẹ̀, ó sọ fún wọn pé: “Ẹ mọ̀ dáadáa bí mo ṣe ń ṣe láàárín yín láti ọjọ́ àkọ́kọ́ tí mo ti dé sí ìpínlẹ̀ Éṣíà,+ 19 tí mò ń sìn bí ẹrú fún Olúwa pẹ̀lú ìrẹ̀lẹ̀*+ àti omijé àti àwọn àdánwò tó ṣẹlẹ̀ sí mi nítorí ọ̀tẹ̀ àwọn Júù, 20 bí mi ò ṣe fà sẹ́yìn nínú sísọ èyíkéyìí lára àwọn ohun tó lérè fún yín* tàbí nínú kíkọ́ yín ní gbangba+ àti láti ilé dé ilé.+ 21 Àmọ́ mo jẹ́rìí kúnnákúnná fún àwọn Júù àti àwọn Gíríìkì nípa ìrònúpìwàdà+ sí Ọlọ́run àti ìgbàgbọ́ nínú Olúwa wa Jésù.+ 22 Ní báyìí, ẹ wò ó! ẹ̀mí ti sọ ọ́ di dandan fún mi,* mò ń rin ìrìn àjò lọ sí Jerúsálẹ́mù, bó tilẹ̀ jẹ́ pé mi ò mọ ohun tó máa ṣẹlẹ̀ sí mi níbẹ̀, 23 kìkì pé ẹ̀mí mímọ́ ń jẹ́rìí fún mi léraléra láti ìlú dé ìlú pé ẹ̀wọ̀n àti ìpọ́njú ń dúró dè mí.+ 24 Síbẹ̀, mi ò ka ẹ̀mí* mi sí ohun tó ṣe pàtàkì* sí mi, tí mo bá ṣáà ti lè parí eré ìje mi+ àti iṣẹ́ òjíṣẹ́ tí mo gbà lọ́wọ́ Jésù Olúwa, láti jẹ́rìí kúnnákúnná sí ìhìn rere nípa inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Ọlọ́run.

25 “Ní báyìí, ẹ wò ó! Mo mọ̀ pé kò sí ìkankan nínú ẹ̀yin tí mo wàásù Ìjọba náà fún tó máa tún rí ojú mi mọ́. 26 Torí náà, mo pè yín ṣe ẹlẹ́rìí lónìí yìí pé ọrùn mi mọ́ kúrò nínú ẹ̀jẹ̀ gbogbo èèyàn,+ 27 nítorí mi ò fà sẹ́yìn nínú sísọ gbogbo ìpinnu Ọlọ́run* fún yín.+ 28 Ẹ kíyè sí ara yín+ àti gbogbo agbo, láàárín èyí tí ẹ̀mí mímọ́ ti yàn yín ṣe alábòójútó,+ láti ṣe olùṣọ́ àgùntàn ìjọ Ọlọ́run,+ èyí tí ó fi ẹ̀jẹ̀ Ọmọ òun fúnra rẹ̀ rà.+ 29 Mo mọ̀ pé lẹ́yìn tí mo bá lọ, àwọn aninilára ìkookò máa wọlé sáàárín yín,+ wọn ò sì ní fọwọ́ pẹ̀lẹ́ mú agbo, 30 àwọn kan máa dìde láàárín yín, wọ́n á sọ àwọn ọ̀rọ̀ békebèke láti fa àwọn ọmọ ẹ̀yìn sẹ́yìn ara wọn.+

31 “Nítorí náà, ẹ máa wà lójúfò, kí ẹ sì fi sọ́kàn pé fún ọdún mẹ́ta,+ mi ò ṣíwọ́ gbígba ẹnì kọ̀ọ̀kan yín níyànjú pẹ̀lú omijé tọ̀sántòru. 32 Ní báyìí, mo fà yín lé ọwọ́ Ọlọ́run àti ọ̀rọ̀ inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí rẹ̀, ọ̀rọ̀ tí ó lè gbé yín ró, kí ó sì fún yín ní ogún náà láàárín gbogbo àwọn tí a sọ di mímọ́.+ 33 Fàdákà tàbí wúrà tàbí aṣọ èèyàn kankan ò wọ̀ mí lójú.+ 34 Ẹ̀yin fúnra yín mọ̀ pé àwọn ọwọ́ yìí ti pèsè àwọn ohun tí mo nílò+ àti àwọn ohun tí àwọn tó wà pẹ̀lú mi nílò. 35 Mo ti fi hàn yín nínú ohun gbogbo nípa ṣíṣe iṣẹ́ kára lọ́nà yìí+ pé, ẹ gbọ́dọ̀ ṣèrànwọ́ fún àwọn tó jẹ́ aláìlera, ẹ sì gbọ́dọ̀ fi àwọn ọ̀rọ̀ Jésù Olúwa sọ́kàn, nígbà tí òun fúnra rẹ̀ sọ pé: ‘Ayọ̀ púpọ̀ wà nínú fífúnni+ ju èyí tó wà nínú rírígbà lọ.’”

36 Nígbà tó sọ àwọn nǹkan yìí tán, ó kúnlẹ̀ pẹ̀lú gbogbo wọn, ó sì gbàdúrà. 37 Ní tòótọ́, gbogbo wọn bú sẹ́kún, wọ́n gbá Pọ́ọ̀lù mọ́ra,* wọ́n sì fẹnu kò ó lẹ́nu tìfẹ́tìfẹ́,* 38 torí ọ̀rọ̀ tó sọ, pé wọn ò ní rí ojú òun mọ́,+ dùn wọ́n wọra. Lẹ́yìn náà, wọ́n sìn ín dé ìdí ọkọ̀ òkun.

21 Lẹ́yìn tí a já ara wa gbà lọ́wọ́ wọn, tí a sì wọkọ̀ òkun, a lọ tààrà, a sì dé Kọ́sì, ní ọjọ́ kejì a lọ sí Ródésì, láti ibẹ̀ a lọ sí Pátárà. 2 Nígbà tí a rí ọkọ̀ òkun kan tó ń sọdá lọ sí Foníṣíà, a wọ̀ ọ́, ó sì gbéra. 3 Bí a ṣe ń wo erékùṣù Sápírọ́sì lọ́ọ̀ọ́kán, a fi í sílẹ̀ sẹ́yìn ní apá òsì,* ọkọ̀ wa forí lé Síríà, a sì gúnlẹ̀ sí Tírè, níbi tí ọkọ̀ náà ti máa já ẹrù rẹ̀. 4 A wá àwọn ọmọ ẹ̀yìn, a rí wọn, a sì lo ọjọ́ méje níbẹ̀. Àmọ́ nítorí ohun tí ẹ̀mí mímọ́ fi hàn wọ́n, léraléra ni wọ́n sọ fún Pọ́ọ̀lù pé kó má ṣe fẹsẹ̀ kan Jerúsálẹ́mù.+ 5 Torí náà, nígbà tí àkókò tí a fẹ́ lò níbẹ̀ pé, a kúrò níbẹ̀, a sì bẹ̀rẹ̀ ìrìn àjò wa, àmọ́ gbogbo wọn, pẹ̀lú àwọn obìnrin àti àwọn ọmọdé, sìn wá títí a fi jáde nínú ìlú náà. A kúnlẹ̀ ní etíkun, a gbàdúrà, 6 a sì dágbére fún ara wa. A lọ wọkọ̀ òkun, àwọn náà sì pa dà sílé wọn.

7 Lẹ́yìn náà, ọkọ̀ òkun wa kúrò ní Tírè, a sì dé Tólémáísì, a kí àwọn ará, a sì lo ọjọ́ kan lọ́dọ̀ wọn. 8 Lọ́jọ́ kejì, a gbéra, a sì dé Kesaríà, a wọ ilé Fílípì ajíhìnrere, tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ọkùnrin méje + náà, a sì dúró lọ́dọ̀ rẹ̀. 9 Ọkùnrin yìí ní àwọn ọmọbìnrin mẹ́rin tí kò tíì lọ́kọ,* tí wọ́n ń sọ tẹ́lẹ̀.+ 10 Àmọ́ lẹ́yìn tí a lo ọjọ́ mélòó kan níbẹ̀, wòlíì kan tó ń jẹ́ Ágábù+ wá láti Jùdíà. 11 Ó wá sọ́dọ̀ wa, ó mú àmùrè Pọ́ọ̀lù, ó sì de ẹsẹ̀ àti ọwọ́ ara rẹ̀, ó sọ pé: “Ohun tí ẹ̀mí mímọ́ sọ nìyí, ‘Bí àwọn Júù ṣe máa di ọkùnrin tí àmùrè yìí jẹ́ tirẹ̀ nìyí ní Jerúsálẹ́mù,+ wọ́n á sì fà á lé ọwọ́ àwọn èèyàn orílẹ̀-èdè.’”+ 12 Tóò, nígbà tí a gbọ́ ọ̀rọ̀ yìí, àwa àti àwọn tó wà níbẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í bẹ̀ ẹ́ pé kó má lọ sí Jerúsálẹ́mù. 13 Ni Pọ́ọ̀lù bá fèsì pé: “Kí ni ẹ̀ ń ṣe yìí, tí ẹ̀ ń sunkún, tí ẹ sì fẹ́ kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá mi?* Ẹ jẹ́ kó dá yín lójú pé, mo ti múra tán láti kú ní Jerúsálẹ́mù nítorí orúkọ Jésù Olúwa,+ kì í ṣe pé kí wọ́n kàn dè mí nìkan ni.” 14 Nígbà tí a ò lè yí i lérò pa dà, a fi í sílẹ̀,* a sọ pé: “Kí ìfẹ́ Jèhófà* ṣẹ.”

15 Lẹ́yìn ìgbà yẹn, a múra ìrìn àjò, a sì bọ́ sọ́nà, ó di Jerúsálẹ́mù. 16 Lára àwọn ọmọ ẹ̀yìn láti Kesaríà náà bá wa lọ, wọ́n mú wa lọ sọ́dọ̀ Mínásónì ará Sápírọ́sì, ọ̀kan lára àwọn tó kọ́kọ́ di ọmọ ẹ̀yìn, ilé rẹ̀ ni wọ́n fẹ́ fi wá sí. 17 Nígbà tí a dé Jerúsálẹ́mù, àwọn ará gbà wá tayọ̀tayọ̀. 18 Àmọ́ lọ́jọ́ tó tẹ̀ lé e, Pọ́ọ̀lù tẹ̀ lé wa lọ sọ́dọ̀ Jémíìsì,+ gbogbo àwọn alàgbà sì wà níbẹ̀. 19 Ó kí wọn, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í ròyìn kúlẹ̀kúlẹ̀ àwọn ohun tí Ọlọ́run ṣe láàárín àwọn orílẹ̀-èdè nípasẹ̀ iṣẹ́ òjíṣẹ́ tí ó ṣe.

20 Lẹ́yìn tí wọ́n gbọ́ ọ̀rọ̀ yìí, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í yin Ọlọ́run lógo, àmọ́ wọ́n sọ fún un pé: “Arákùnrin, wo bí ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn onígbàgbọ́ tó wà láàárín àwọn Júù ṣe pọ̀ tó, gbogbo wọn ló sì ní ìtara fún Òfin.+ 21 Àmọ́ wọ́n ti gbọ́ àhesọ nípa rẹ pé ò ń kọ́ gbogbo Júù tó wà láàárín àwọn orílẹ̀-èdè pé kí wọ́n kẹ̀yìn sí Mósè, tí ò ń sọ fún wọn pé kí wọ́n má ṣe dádọ̀dọ́* àwọn ọmọ wọn tàbí tẹ̀ lé àwọn àṣà wọn.+ 22 Kí wá ni ṣíṣe lórí ọ̀rọ̀ yìí? Ó dájú pé wọ́n á gbọ́ pé o ti dé. 23 Torí náà, ṣe ohun tí a bá sọ fún ọ: Ọkùnrin mẹ́rin wà lọ́dọ̀ wa tí wọ́n ti jẹ́jẹ̀ẹ́. 24 Mú àwọn ọkùnrin yìí dání, kí o wẹ ara rẹ mọ́ pẹ̀lú wọn lọ́nà Òfin, kí o sì bójú tó ìnáwó wọn, kí wọ́n lè fá orí wọn. Nígbà náà, gbogbo èèyàn á mọ̀ pé kò sí òótọ́ kankan nínú àwọn ọ̀rọ̀ àhesọ tí wọ́n ń gbọ́ nípa rẹ, àmọ́ pé ò ń rìn létòlétò àti pé ìwọ náà ń pa Òfin mọ́.+ 25 Ní ti àwọn onígbàgbọ́ tó wá látinú àwọn orílẹ̀-èdè, a ti kọ ìpinnu wa ránṣẹ́ sí wọn pé kí wọ́n yẹra fún ohun tí wọ́n fi rúbọ sí àwọn òrìṣà,+ kí wọ́n yẹra fún ẹ̀jẹ̀,+ fún ohun tí wọ́n fún lọ́rùn pa*+ àti ìṣekúṣe.”*+

26 Lẹ́yìn náà, Pọ́ọ̀lù mú àwọn ọkùnrin náà dání ní ọjọ́ kejì, ó sì wẹ ara rẹ̀ mọ́ pẹ̀lú wọn lọ́nà Òfin,+ ó wọ tẹ́ńpìlì lọ láti sọ ìgbà tí àwọn ọjọ́ ìwẹ̀mọ́ náà máa parí, kí àlùfáà lè rú ẹbọ fún ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn.

27 Nígbà tó kù díẹ̀ kí ọjọ́ méje náà pé, àwọn Júù tó wá láti Éṣíà rí i nínú tẹ́ńpìlì, ni wọ́n bá ru gbogbo èrò lọ́kàn sókè, wọ́n sì gbá a mú, 28 wọ́n ń kígbe pé: “Ẹ̀yin èèyàn Ísírẹ́lì, ẹ gbà wá o! Ọkùnrin tó ń kọ́ gbogbo èèyàn níbi gbogbo láti kẹ̀yìn sí àwọn èèyàn wa àti sí Òfin àti sí ibí yìí ti dé síbí o. Yàtọ̀ síyẹn, ó tún mú àwọn Gíríìkì wá sínú tẹ́ńpìlì, ó sì ti sọ ibi mímọ́ yìí di ẹlẹ́gbin.”+ 29 Nítorí wọ́n ti rí Tírófímù+ ará Éfésù pẹ̀lú rẹ̀ nínú ìlú náà tẹ́lẹ̀, wọ́n sì rò pé Pọ́ọ̀lù mú un wọ inú tẹ́ńpìlì. 30 Gbogbo ìlú náà dà rú, àwọn èèyàn rọ́ wá, wọ́n gbá Pọ́ọ̀lù mú, wọ́n sì wọ́ ọ lọ sẹ́yìn tẹ́ńpìlì, lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, wọ́n ti àwọn ilẹ̀kùn. 31 Bí wọ́n ṣe fẹ́ pa á, ọ̀gágun àwùjọ ọmọ ogun gbọ́ pé gbogbo Jerúsálẹ́mù ti dà rú; 32 lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, ó kó àwọn ọmọ ogun àti àwọn ọ̀gá ọmọ ogun lẹ́yìn, wọ́n sì sáré lọ bá wọn. Nígbà tí wọ́n tajú kán rí ọ̀gágun náà àti àwọn ọmọ ogun, wọ́n ṣíwọ́ lílu Pọ́ọ̀lù.

33 Ọ̀gágun wá sún mọ́ wọn, ó mú un, ó sì pàṣẹ pé kí wọ́n fi ẹ̀wọ̀n méjì dè é;+ lẹ́yìn náà, ó wádìí ẹni tó jẹ́ àti ohun tó ṣe. 34 Àmọ́, bí àwọn kan láàárín èrò náà ṣe ń pariwo ohun kan, bẹ́ẹ̀ ni àwọn míì ń pariwo ohun míì. Torí náà, ó ní kí wọ́n mú un wá sí ibùdó àwọn ọmọ ogun, torí ariwo wọn kò jẹ́ kó mọ ohun tó ṣẹlẹ̀ gan-an. 35 Àmọ́ nígbà tó dé orí àtẹ̀gùn, àwọn ọmọ ogun ní láti gbé e nítorí ìwà ipá àwọn èrò náà, 36 torí ṣe ni ọ̀pọ̀ èèyàn ń tẹ̀ lé wọn, tí wọ́n ń kígbe pé: “Ẹ pa á dà nù!”

37 Bí wọ́n ṣe fẹ́ mú Pọ́ọ̀lù wọ ibùdó àwọn ọmọ ogun, ó béèrè lọ́wọ́ ọ̀gágun náà pé: “Ṣé mo lè sọ nǹkan kan fún ọ?” Ó fèsì pé: “Ṣé o lè sọ èdè Gíríìkì? 38 Ìwọ kọ́ ni ará Íjíbítì tó dáná ọ̀tẹ̀ sí ìjọba ní ìjelòó, tó sì kó ẹgbẹ̀rún mẹ́rin (4,000) ọkùnrin ọlọ́bẹ aṣóró jáde lọ sí aginjù?” 39 Pọ́ọ̀lù wá sọ pé: “Ní tòótọ́, Júù ni mí,+ láti Tásù+ ní Sìlíṣíà, ọmọ ìlú kan tó gbajúmọ̀.* Torí náà, mo bẹ̀ ọ́, jẹ́ kí n bá àwọn èèyàn náà sọ̀rọ̀.” 40 Lẹ́yìn tó gbà á láyè, Pọ́ọ̀lù dúró lórí àtẹ̀gùn náà, ó ju ọwọ́ sí àwọn èèyàn náà. Nígbà tí kẹ́kẹ́ pa, ó bá wọn sọ̀rọ̀ ní èdè Hébérù,+ ó ní:

22 “Ẹ̀yin èèyàn, ẹ̀yin ará àti ẹ̀yin bàbá, ẹ gbọ́ ẹjọ́ tí mo fẹ́ rò fún yín.”+ 2 Tóò, nígbà tí wọ́n gbọ́ pé ó ń bá wọn sọ̀rọ̀ ní èdè Hébérù, wọ́n túbọ̀ dákẹ́, ó sì sọ pé: 3 “Júù+ ni mí, ìlú Tásù ní Sìlíṣíà+ ni wọ́n ti bí mi, àmọ́ ìlú yìí ni mo ti gba ẹ̀kọ́ lọ́dọ̀* Gàmálíẹ́lì,+ wọ́n fi Òfin àwọn baba ńlá ìgbàanì dá mi lẹ́kọ̀ọ́ lọ́nà àìgbagbẹ̀rẹ́,+ mo sì jẹ́ onítara fún Ọlọ́run bí gbogbo yín ṣe jẹ́ lónìí yìí.+ 4 Mo ṣe inúnibíni sí àwọn tó ń tẹ̀ lé Ọ̀nà yìí tí wọ́n fi kú, bí mo ṣe ń de tọkùnrin tobìnrin tí mo sì ń jù wọ́n sẹ́wọ̀n,+ 5 àlùfáà àgbà àti gbogbo àpéjọ àwọn àgbààgbà náà lè jẹ́rìí sí i. Mó tún gba àwọn lẹ́tà látọwọ́ wọn lọ sọ́dọ̀ àwọn ará ní Damásíkù, mo sì bọ́ sójú ọ̀nà kí n lè lọ mú àwọn tó wà níbẹ̀ wá sí Jerúsálẹ́mù ní dídè láti fìyà jẹ wọ́n.

6 “Àmọ́ bí mo ṣe ń rin ìrìn àjò lọ, tí mo sì ń sún mọ́ Damásíkù, ní ọ̀sán gangan, ìmọ́lẹ̀ ńlá kan láti ọ̀run kọ mànà lójijì yí mi ká,+ 7 mo bá ṣubú lulẹ̀, mo sì gbọ́ ohùn kan tó sọ fún mi pé: ‘Sọ́ọ̀lù, Sọ́ọ̀lù, kí nìdí tí o fi ń ṣe inúnibíni sí mi?’ 8 Mo fèsì pé: ‘Ta ni ọ́, Olúwa?’ Ó wá sọ fún mi pé: ‘Èmi ni Jésù ará Násárẹ́tì, ẹni tí ò ń ṣe inúnibíni sí.’ 9 Lákòókò yìí, àwọn tó wà pẹ̀lú mi rí ìmọ́lẹ̀ náà, àmọ́ wọn ò gbọ́ ohùn ẹni tó ń bá mi sọ̀rọ̀. 10 Ni mo bá sọ pé: ‘Kí ni kí n ṣe, Olúwa?’ Olúwa sọ fún mi pé: ‘Dìde, lọ sínú Damásíkù, ibẹ̀ ni wọ́n á ti sọ ohun gbogbo tí a ti yàn fún ọ láti ṣe.’+ 11 Àmọ́ nítorí pé ògo ìmọ́lẹ̀ náà kò jẹ́ kí n rí nǹkan kan, ṣe ni àwọn tó wà pẹ̀lú mi fà mí lọ́wọ́ dé Damásíkù.

12 “Ni ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Ananáyà, onífọkànsìn tó ń pa Òfin mọ́, tí gbogbo àwọn Júù tó ń gbé ibẹ̀ ròyìn rẹ̀ dáadáa, 13 bá wá sọ́dọ̀ mi. Ó dúró sẹ́gbẹ̀ẹ́ mi, ó sì sọ fún mi pé: ‘Sọ́ọ̀lù, arákùnrin, pa dà ríran!’ Ní àkókò yẹn gan-an, mo gbójú sókè, mo sì rí i.+ 14 Ó sọ pé: ‘Ọlọ́run àwọn baba ńlá wa ti yàn ọ́ láti wá mọ ìfẹ́ rẹ̀, láti rí olódodo náà+ àti láti gbọ́ ohùn ẹnu rẹ̀, 15 torí o máa jẹ́ ẹlẹ́rìí rẹ̀ láti sọ ohun tí o ti rí, tí o sì ti gbọ́+ fún gbogbo èèyàn. 16 Ní báyìí, kí lò ń dúró dè? Dìde, kí o ṣèrìbọmi, kí o sì wẹ àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ+ nù nípa kíké pe orúkọ rẹ̀.’+

17 “Àmọ́ nígbà tí mo pa dà sí Jerúsálẹ́mù,+ tí mo sì ń gbàdúrà nínú tẹ́ńpìlì, mo bọ́ sójú ìran, 18 mo sì rí i tí ó sọ fún mi pé: ‘Ṣe kíá, kí o sì tètè jáde kúrò ní Jerúsálẹ́mù, torí pé wọn ò ní gba ẹ̀rí tí o máa jẹ́ nípa mi.’+ 19 Mo wá sọ pé: ‘Olúwa, àwọn fúnra wọn mọ̀ dáadáa pé mo máa ń ju àwọn tó gbà ọ́ gbọ́ sẹ́wọ̀n, mo sì máa ń nà wọ́n lẹ́gba láti sínágọ́gù kan dé òmíràn;+ 20 nígbà tí wọ́n ń ta ẹ̀jẹ̀ Sítéfánù ẹlẹ́rìí rẹ sílẹ̀, mo wà níbẹ̀, mo fọwọ́ sí i, mo sì ń ṣọ́ aṣọ àwọ̀lékè àwọn tí ó pa á.’+ 21 Síbẹ̀, ó sọ fún mi pé: ‘Lọ, nítorí màá rán ọ sí àwọn orílẹ̀-èdè tó jìnnà réré.’”+

22 Wọ́n ń fetí sí i títí dórí ọ̀rọ̀ yìí. Wọ́n sì gbé ohùn wọn sókè, wọ́n ní: “Ẹ mú irú ọkùnrin yìí kúrò láyé, torí kò yẹ kó wà láàyè!” 23 Nítorí pé wọ́n ń kígbe, wọ́n ń ju aṣọ àwọ̀lékè wọn káàkiri, wọ́n sì ń da iyẹ̀pẹ̀ sókè,+ 24 ọ̀gágun náà pàṣẹ pé kí wọ́n mú Pọ́ọ̀lù wá sí ibùdó àwọn ọmọ ogun, ó sì ní kí wọ́n nà án láti wádìí lọ́wọ́ rẹ̀, kí ó lè mọ ohun tó fà á gan-an tí wọ́n fi ń pariwo lé Pọ́ọ̀lù lórí lọ́nà yìí. 25 Àmọ́ nígbà tí wọ́n ti na Pọ́ọ̀lù tàntàn láti nà án lẹ́gba, ó sọ fún ọ̀gá ọmọ ogun tó dúró níbẹ̀ pé: “Ṣé ó bófin mu fún yín láti na ará Róòmù* tí wọn ò tíì dá lẹ́bi lẹ́gba?”*+ 26 Tóò, nígbà tí ọ̀gá ọmọ ogun náà gbọ́ ọ̀rọ̀ yìí, ó lọ bá ọ̀gágun, ó sì ròyìn fún un pé: “Kí lo fẹ́ ṣe yìí? Ará Róòmù mà ni ọkùnrin yìí.” 27 Ni ọ̀gágun náà bá sún mọ́ Pọ́ọ̀lù, ó ní: “Sọ fún mi, Ṣé ará Róòmù ni ọ́?” Ó sọ pé: “Bẹ́ẹ̀ ni.” 28 Ọ̀gágun náà wá sọ pé: “Owó gọbọi ni mo fi ra ẹ̀tọ́ ọmọ ìbílẹ̀ Róòmù.” Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Wọ́n bí èmi síbẹ̀ ni.”+

29 Torí náà, ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ni àwọn tó fẹ́ fi ìdálóró wádìí ọ̀rọ̀ lẹ́nu rẹ̀ fi í sílẹ̀; ẹ̀rù sì ba ọ̀gágun náà nígbà tí ó mọ̀ pé ará Róòmù ni, torí pé ó ti fi ṣẹkẹ́ṣẹkẹ̀ dè é.+

30 Ní ọjọ́ kejì, ó tú u sílẹ̀ nítorí ó fẹ́ rí àrídájú ohun tó fà á tí àwọn Júù fi ń fẹ̀sùn kàn án, ó pàṣẹ pé kí àwọn olórí àlùfáà àti gbogbo Sàhẹ́ndìrìn pé jọ. Lẹ́yìn náà, ó mú Pọ́ọ̀lù sọ̀ kalẹ̀, ó sì mú un dúró láàárín wọn.+

23 Bí Pọ́ọ̀lù ṣe tẹjú mọ́ Sàhẹ́ndìrìn, ó sọ pé: “Ẹ̀yin èèyàn, ẹ̀yin ará, mo ti hùwà níwájú Ọlọ́run pẹ̀lú ẹ̀rí ọkàn tó mọ́ láìkù síbì kan+ títí di òní yìí.” 2 Ni Ananáyà àlùfáà àgbà bá pàṣẹ fún àwọn tó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀ pé kí wọ́n gbá a lẹ́nu. 3 Nígbà náà, Pọ́ọ̀lù sọ fún un pé: “Ọlọ́run yóò gbá ọ, ìwọ ògiri tí a kùn lẹ́fun. Ṣebí torí kí o lè fi Òfin ṣèdájọ́ mi lo ṣe jókòó, kí ló dé tí ìwọ fúnra rẹ tún ń rú Òfin bí o ṣe ní kí wọ́n gbá mi?” 4 Ni àwọn tó wà níbẹ̀ bá sọ pé: “Ṣé ò ń bú àlùfáà àgbà Ọlọ́run ni?” 5 Pọ́ọ̀lù fèsì pé: “Ẹ̀yin ará, mi ò mọ̀ pé àlùfáà àgbà ni. Nítorí ó wà lákọsílẹ̀ pé, ‘O ò gbọ́dọ̀ sọ̀rọ̀ alákòóso àwọn èèyàn rẹ láìdáa.’”+

6 Nígbà tí Pọ́ọ̀lù rí i pé apá kan wọn jẹ́ Sadusí, àwọn tó kù sì jẹ́ Farisí, ó ké jáde ní Sàhẹ́ndìrìn pé: “Ẹ̀yin èèyàn, ẹ̀yin ará, Farisí ni mí,+ mo sì jẹ́ ọmọ àwọn Farisí. Torí ìrètí àjíǹde àwọn òkú ni wọ́n ṣe ń dá mi lẹ́jọ́.” 7 Nítorí ohun tó sọ yìí, ìyapa dé sáàárín àwọn Farisí àti àwọn Sadusí, àpéjọ náà sì pín sí méjì. 8 Torí àwọn Sadusí sọ pé kò sí àjíǹde tàbí áńgẹ́lì tàbí ẹ̀mí, àmọ́ àwọn Farisí gbà pé gbogbo wọn wà.*+ 9 Nítorí náà, ariwo ńlá sọ, lára àwọn akọ̀wé òfin tí wọ́n wà nínú ẹgbẹ́ àwọn Farisí dìde, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í jiyàn kíkankíkan, wọ́n ń sọ pé: “A ò rí ohun àìtọ́ kankan tí ọkùnrin yìí ṣe, àmọ́ tí ẹ̀mí tàbí áńgẹ́lì bá bá a sọ̀rọ̀+ —.” 10 Nígbà tí ọ̀rọ̀ náà di rannto, ẹ̀rù ba ọ̀gágun pé wọ́n á fa Pọ́ọ̀lù ya, ló bá pàṣẹ pé kí àwọn ọmọ ogun sọ̀ kalẹ̀, kí wọ́n já a gbà kúrò láàárín wọn, kí wọ́n sì mú un wá sí ibùdó àwọn ọmọ ogun.

11 Àmọ́ ní òru ọjọ́ náà, Olúwa dúró lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀, ó sì sọ pé: “Mọ́kàn le!+ Nítorí pé bí o ṣe ń jẹ́rìí kúnnákúnná nípa mi ní Jerúsálẹ́mù, bẹ́ẹ̀ lo ṣe máa jẹ́rìí ní Róòmù.”+

12 Nígbà tí ilẹ̀ mọ́, àwọn Júù gbìmọ̀ pọ̀, wọ́n sì fi ègún de ara wọn, pé àwọn ò ní jẹ, àwọn ò sì ní mu títí àwọn á fi pa Pọ́ọ̀lù. 13 Ó ju ogójì (40) ọkùnrin tó di ọ̀tẹ̀ oníbùúra yìí. 14 Àwọn ọkùnrin yìí lọ bá àwọn olórí àlùfáà àti àwọn àgbààgbà, wọ́n sì sọ pé: “A ti fi ègún de ara wa* lọ́nà tó rinlẹ̀ láti má ṣe jẹ nǹkan kan títí a ó fi pa Pọ́ọ̀lù. 15 Torí náà, ní báyìí, kí ẹ̀yin pẹ̀lú Sàhẹ́ndìrìn sọ fún ọ̀gágun pé kí ó mú un sọ̀ kalẹ̀ wá sọ́dọ̀ yín bíi pé ẹ fẹ́ túbọ̀ gbé ọ̀rọ̀ rẹ̀ yẹ̀ wò. Àmọ́ kó tó sún mọ́ tòsí, àá ti wà ní sẹpẹ́ láti pa á.”

16 Ṣùgbọ́n, ọmọ arábìnrin Pọ́ọ̀lù gbọ́ pé wọ́n fẹ́ lúgọ de Pọ́ọ̀lù, ló bá wọ ibùdó àwọn ọmọ ogun, ó sì sọ fún Pọ́ọ̀lù. 17 Pọ́ọ̀lù wá pe ọ̀kan lára àwọn ọ̀gá ọmọ ogun, ó sì sọ pé: “Mú ọ̀dọ́kùnrin yìí lọ sọ́dọ̀ ọ̀gágun, torí ó ní ohun kan tó fẹ́ sọ fún un.” 18 Torí náà, ó mú un lọ bá ọ̀gágun, ó sì sọ fún un pé: “Ẹlẹ́wọ̀n tó ń jẹ́ Pọ́ọ̀lù pè mí, ó sì ní kí n mú ọ̀dọ́kùnrin yìí wá bá ọ, torí ó ní ohun kan tó fẹ́ sọ fún ọ.” 19 Ọ̀gágun fà á lọ́wọ́, ó mú un lọ sí kọ̀rọ̀ kan, ó sì bi í pé: “Kí lo fẹ́ sọ fún mi?” 20 Ó sọ pé: “Àwọn Júù ti fohùn ṣọ̀kan pé àwọn á ní kí o mú Pọ́ọ̀lù sọ̀ kalẹ̀ wá sí Sàhẹ́ndìrìn lọ́la bíi pé wọ́n fẹ́ mọ̀ sí i nípa ẹjọ́ rẹ̀.+ 21 Má ṣe gbọ́ tiwọn, torí ó ju ogójì (40) ọkùnrin lára wọn tó lúgọ dè é, wọ́n sì ti fi ègún* de ara wọn pé àwọn ò ní jẹ, àwọn ò sì ní mu títí àwọn á fi pa á;+ wọ́n ti múra tán báyìí, wọ́n ń dúró de àṣẹ látọ̀dọ̀ rẹ.” 22 Nítorí náà, ọ̀gágun ní kí ọ̀dọ́kùnrin náà máa lọ lẹ́yìn tó pàṣẹ fún un pé: “Má sọ fún ẹnikẹ́ni pé o ti sọ nǹkan yìí fún mi.”

23 Ó wá pe méjì lára àwọn ọ̀gá ọmọ ogun, ó sì sọ pé: “Ẹ múra igba (200) ọmọ ogun sílẹ̀ láti lọ sí Kesaríà ní wákàtí kẹta òru,* ẹ tún mú àádọ́rin (70) agẹṣin àti igba (200) àwọn tó ń fọ̀kọ̀ jà dání. 24 Bákan náà, ẹ fún Pọ́ọ̀lù ní àwọn ẹṣin tó máa gbé e dé ọ̀dọ̀ gómìnà Fẹ́líìsì láìséwu.” 25 Ó wá kọ lẹ́tà kan tó lọ báyìí pé:

26 “Kíláúdíù Lísíà sí Ọlọ́lá Jù Lọ, Gómìnà Fẹ́líìsì: Mo kí ọ! 27 Àwọn Júù mú ọkùnrin yìí, wọ́n sì ti fẹ́ pa á, àmọ́ mo tètè wá pẹ̀lú àwọn ọmọ ogun mi, mo sì gbà á sílẹ̀,+ torí mo gbọ́ pé ará Róòmù ni.+ 28 Torí pé mo fẹ́ mọ ìdí tí wọ́n fi ń fẹ̀sùn kàn án, mo mú un sọ̀ kalẹ̀ wá sí Sàhẹ́ndìrìn wọn.+ 29 Mo rí i pé wọ́n fẹ̀sùn kàn án lórí àwọn ọ̀ràn Òfin wọn,+ àmọ́ kò ṣe ohunkóhun tó yẹ fún ikú tàbí fún ìdè. 30 Ṣùgbọ́n nítorí mo gbọ́ pé wọ́n ń gbìmọ̀ pọ̀ láti pa ọkùnrin yìí,+ mò ń fi í ránṣẹ́ sí ọ ní kíákíá, mo sì pàṣẹ fún àwọn tó ń fi ẹ̀sùn kàn án kí wọ́n wá ta kò ó níwájú rẹ.”

31 Nítorí náà, àwọn ọmọ ogun yìí mú Pọ́ọ̀lù+ bí wọ́n ṣe pàṣẹ fún wọn, wọ́n sì mú un wá sí Antipátírísì ní òru. 32 Ní ọjọ́ kejì, wọ́n ní kí àwọn agẹṣin máa mú un lọ, àwọn ọmọ ogun tó kù sì pa dà sí ibùdó àwọn ọmọ ogun. 33 Àwọn agẹṣin náà wọ Kesaríà, wọ́n fi lẹ́tà náà jíṣẹ́ fún gómìnà, wọ́n sì mú Pọ́ọ̀lù wá sọ́dọ̀ rẹ̀. 34 Torí náà, ó kà á, ó béèrè ìpínlẹ̀ tó ti wá, ó sì rí i pé Sìlíṣíà ló ti wá.+ 35 Ó wá sọ pé: “Màá gbọ́ ẹjọ́ rẹ látòkèdélẹ̀ nígbà tí àwọn tó fẹ̀sùn kàn ọ́ bá dé.”+ Ó sì pàṣẹ pé kí wọ́n máa ṣọ́ ọ ní ààfin* Hẹ́rọ́dù.

24 Ọjọ́ márùn-ún lẹ́yìn náà, Ananáyà,+ àlùfáà àgbà wá pẹ̀lú àwọn àgbààgbà kan àti sọ̀rọ̀sọ̀rọ̀* tó ń jẹ́ Tẹ́túlọ́sì, wọ́n sì gbé ẹjọ́ tí wọ́n ní sí Pọ́ọ̀lù wá síwájú gómìnà.+ 2 Nígbà tí wọ́n pè é, Tẹ́túlọ́sì bẹ̀rẹ̀ sí í fẹ̀sùn kàn án, ó ní:

“Bó ṣe jẹ́ pé à ń gbádùn àlàáfíà púpọ̀ nípasẹ̀ rẹ àti pé àròjinlẹ̀ rẹ ń mú kí àwọn àtúnṣe wáyé ní orílẹ̀-èdè yìí, 3 ìgbà gbogbo àti ibi gbogbo la ti ń rí èyí, Fẹ́líìsì Ọlọ́lá Jù Lọ, a dúpẹ́ a tọ́pẹ́ dá. 4 Àmọ́ kí n má bàa gbà ọ́ lákòókò jù, mo bẹ̀ ọ́ nítorí inúure rẹ pé kí o gbọ́ ọ̀rọ̀ wa ní ṣókí. 5 A ti rí i pé alákòóbá* ni ọkùnrin yìí,+ ṣe ló ń dáná ọ̀tẹ̀+ sí ìjọba láàárín gbogbo àwọn Júù káàkiri ilẹ̀ ayé tí à ń gbé, òun sì ni òléwájú nínú ẹ̀ya ìsìn àwọn ará Násárẹ́tì.+ 6 Ó tiẹ̀ tún fẹ́ sọ tẹ́ńpìlì di ẹlẹ́gbin, ìdí nìyẹn tí a fi mú un.+ 7* —— 8 Nígbà tí ìwọ fúnra rẹ bá gbé ọ̀rọ̀ rẹ̀ yẹ̀ wò, gbogbo ẹ̀sùn tí a fi ń kàn án yìí máa ṣe kedere sí ọ.”

9 Ni àwọn Júù náà bá gbè é lẹ́yìn láti ta kò ó, wọ́n ń tẹnu mọ́ ọn pé bẹ́ẹ̀ lọ̀rọ̀ rí. 10 Nígbà tí gómìnà mi orí sí Pọ́ọ̀lù pé kó sọ̀rọ̀, ó fèsì pé:

“Bí mo ṣe mọ̀ dáadáa pé ọ̀pọ̀ ọdún lo ti ń ṣe onídàájọ́ orílẹ̀-èdè yìí, mo ṣe tán láti gbèjà ara mi.+ 11 Ìwọ fúnra rẹ lè wádìí, kò tíì ju ọjọ́ méjìlá (12) tí mo lọ jọ́sìn ní Jerúsálẹ́mù;+ 12 wọn ò sì rí mi pé mò ń bá èèyàn jiyàn nínú tẹ́ńpìlì, àbí pé mo dá àwùjọ onírúgúdù sílẹ̀, yálà nínú àwọn sínágọ́gù tàbí káàkiri ìlú náà. 13 Bẹ́ẹ̀ ni wọn ò lè fún ọ ní ẹ̀rí àwọn ohun tí wọ́n ń fẹ̀sùn rẹ̀ kàn mí yìí. 14 Àmọ́ mo fẹ́ sọ fún ọ pé, ọ̀nà tí wọ́n ń pè ní ẹ̀ya ìsìn yìí ni mo gbà ń ṣe iṣẹ́ ìsìn mímọ́ fún Ọlọ́run àwọn baba ńlá mi,+ torí mo gba gbogbo ohun tó wà nínú Òfin gbọ́ àti ohun tó wà lákọsílẹ̀ nínú ìwé àwọn Wòlíì.+ 15 Mo ní ìrètí nínú Ọlọ́run, ìrètí tí àwọn ọkùnrin yìí náà ní, pé àjíǹde+ àwọn olódodo àti àwọn aláìṣòdodo+ yóò wà. 16 Nítorí èyí, ìgbà gbogbo ni mo máa ń fẹ́ kí ẹ̀rí ọkàn mi mọ́* níwájú Ọlọ́run àti èèyàn.+ 17 Tóò, lẹ́yìn ọ̀pọ̀ ọdún, mo dé láti mú ọrẹ àánú+ wá fún orílẹ̀-èdè mi, kí n sì mú àwọn ọrẹ wá pẹ̀lú. 18 Bí mo ṣe ń ṣe àwọn nǹkan yìí lọ́wọ́, wọ́n rí i pé mo wà ní mímọ́ lọ́nà Òfin nínú tẹ́ńpìlì,+ àmọ́ kì í ṣe pé mo kó èrò lẹ́yìn, àbí pé mò ń dá wàhálà sílẹ̀. Àwọn Júù kan láti ìpínlẹ̀ Éṣíà wà níbẹ̀, 19 tó yẹ kí wọ́n wà níwájú rẹ níbí, kí wọ́n wá fẹ̀sùn kàn mí tí wọ́n bá ní ohunkóhun lòdì sí mi.+ 20 Tàbí kẹ̀, kí àwọn ọkùnrin tó wà níbí yìí fúnra wọn sọ ohun àìtọ́ tí wọ́n rí nígbà tí mo dúró níwájú Sàhẹ́ndìrìn, 21 àyàfi ohun kan ṣoṣo yìí tí mo ké jáde nígbà tí mo dúró láàárín wọn, pé: ‘Torí àjíǹde àwọn òkú ni wọ́n ṣe ń dá mi lẹ́jọ́ lónìí níwájú yín!’”+

22 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Fẹ́líìsì mọ̀ nípa Ọ̀nà + yìí dáadáa, ó sún ẹjọ́ àwọn ọkùnrin náà síwájú, ó sọ pé: “Nígbàkigbà tí Lísíà ọ̀gágun bá wá síbí, màá ṣe ìpinnu lórí ọ̀ràn yín.” 23 Ó wá pàṣẹ fún ọ̀gá àwọn ọmọ ogun pé kí wọ́n fi ọkùnrin náà sí àhámọ́, àmọ́ kí wọ́n fún un ní òmìnira díẹ̀, kí wọ́n sì gba àwọn èèyàn rẹ̀ láyè láti máa bá a ṣe ohun tó bá fẹ́ ṣe.

24 Ọjọ́ mélòó kan lẹ́yìn náà, Fẹ́líìsì dé pẹ̀lú Dùrùsílà ìyàwó rẹ̀ tó jẹ́ Júù, ó ránṣẹ́ pe Pọ́ọ̀lù, ó sì ń fetí sí i bó ṣe ń sọ̀rọ̀ nípa ìgbàgbọ́ nínú Kristi Jésù.+ 25 Àmọ́ bí Pọ́ọ̀lù ṣe sọ̀rọ̀ nípa òdodo àti ìkóra-ẹni-níjàánu pẹ̀lú ìdájọ́ tó ń bọ̀,+ ẹ̀rù ba Fẹ́líìsì, ó sì fèsì pé: “Ṣì máa lọ ná, màá ránṣẹ́ pè ẹ́ nígbà míì tí mo bá ráyè.” 26 Lẹ́sẹ̀ kan náà, ó ń retí pé Pọ́ọ̀lù máa fún òun lówó. Torí ìyẹn, lemọ́lemọ́ ló ń ránṣẹ́ pè é, tó sì ń bá a sọ̀rọ̀. 27 Lẹ́yìn ọdún méjì, Pọ́kíọ́sì Fẹ́sítọ́ọ̀sì rọ́pò Fẹ́líìsì; àmọ́ torí pé Fẹ́líìsì ń wá ojú rere àwọn Júù,+ ó fi Pọ́ọ̀lù sílẹ̀ nínú àhámọ́.

25 Nítorí náà, lẹ́yìn tí Fẹ́sítọ́ọ̀sì+ dé ìpínlẹ̀ náà, tó sì bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́, ó kúrò ní Kesaríà lẹ́yìn ọjọ́ kẹta, ó sì lọ sí Jerúsálẹ́mù. 2 Àwọn olórí àlùfáà àti àwọn èèyàn sàràkí-sàràkí lára àwọn Júù wá sọ̀rọ̀ Pọ́ọ̀lù láìdáa lójú rẹ̀.+ Torí náà, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í bẹ Fẹ́sítọ́ọ̀sì 3 pé kó ṣojú rere sáwọn,* kó ránṣẹ́ pe Pọ́ọ̀lù wá sí Jerúsálẹ́mù. Àmọ́ ṣe ni wọ́n ń gbèrò láti lúgọ de Pọ́ọ̀lù kí wọ́n sì pa á lójú ọ̀nà.+ 4 Ṣùgbọ́n, Fẹ́sítọ́ọ̀sì fèsì pé kí wọ́n fi Pọ́ọ̀lù sílẹ̀ nínú àhámọ́ ní Kesaríà pé òun náà máa pa dà síbẹ̀ láìpẹ́. 5 Ó sọ pé: “Torí náà, kí àwọn tó wà nípò àṣẹ láàárín yín bá mi lọ, kí wọ́n sì fẹ̀sùn kàn án, tó bá jẹ́ pé òótọ́ ni ọkùnrin náà ti ṣe ohun tí kò tọ́.”+

6 Nígbà tó ti lo nǹkan bí ọjọ́ mẹ́jọ sí mẹ́wàá láàárín wọn, ó lọ sí Kesaríà, ó jókòó sórí ìjókòó ìdájọ́ lọ́jọ́ kejì, ó sì pàṣẹ pé kí wọ́n mú Pọ́ọ̀lù wọlé. 7 Nígbà tó wọlé, àwọn Júù tó wá láti Jerúsálẹ́mù dúró yí i ká, wọ́n ń fi ọ̀pọ̀ ẹ̀sùn tó lágbára kàn án, àwọn ẹ̀sùn tí wọn kò lè fi ẹ̀rí rẹ̀ hàn.+

8 Àmọ́ Pọ́ọ̀lù gbèjà ara rẹ̀, ó ní: “Mi ò dá ẹ̀ṣẹ̀ kankan sí Òfin àwọn Júù tàbí sí tẹ́ńpìlì tàbí sí Késárì.”+ 9 Fẹ́sítọ́ọ̀sì, tó ń wá ojú rere àwọn Júù,+ dá Pọ́ọ̀lù lóhùn pé: “Ṣé o fẹ́ lọ sí Jerúsálẹ́mù, kí a lè dá ẹjọ́ rẹ níbẹ̀ níwájú mi lórí àwọn nǹkan yìí?” 10 Àmọ́ Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Mo dúró níwájú ìjókòó ìdájọ́ Késárì, níbi tó yẹ kí a ti dá ẹjọ́ mi. Mi ò ṣe àìdáa kankan sí àwọn Júù, bí ìwọ náà ṣe ń rí i kedere báyìí. 11 Tó bá jẹ́ pé oníwà àìtọ́ ni mí lóòótọ́, tí mo sì ti ṣe ohun tó yẹ fún ikú,+ mi ò bẹ̀bẹ̀ pé kí ẹ má pa mí; àmọ́ tí kò bá sí òótọ́ nínú gbogbo ẹ̀sùn tí àwọn ọkùnrin yìí fi kàn mí, kò sẹ́ni tó lẹ́tọ̀ọ́ láti fi mí lé wọn lọ́wọ́ kó lè fi wá ojú rere. Mo ké gbàjarè sí Késárì!”+ 12 Lẹ́yìn tí Fẹ́sítọ́ọ̀sì ti bá àwùjọ àwọn agbani-nímọ̀ràn sọ̀rọ̀, ó fèsì pé: “Késárì lo ké gbàjarè sí; ọ̀dọ̀ Késárì ni wàá sì lọ.”

13 Lẹ́yìn ọjọ́ mélòó kan, Ọba Ágírípà àti Bẹ̀níìsì dé sí Kesaríà láti ṣe ìbẹ̀wò àyẹ́sí sọ́dọ̀ Fẹ́sítọ́ọ̀sì. 14 Nítorí pé wọ́n máa pẹ́ díẹ̀ níbẹ̀, Fẹ́sítọ́ọ̀sì gbé ẹjọ́ Pọ́ọ̀lù wá síwájú ọba, ó ní:

“Ọkùnrin kan wà tí Fẹ́líìsì fi sílẹ̀ nínú ẹ̀wọ̀n, 15 nígbà tí mo wà ní Jerúsálẹ́mù, àwọn olórí àlùfáà àti àwọn àgbààgbà Júù sọ ọ̀rọ̀ rẹ̀ fún mi,+ wọ́n ní kí a dá a lẹ́bi. 16 Àmọ́ mo fún wọn lésì pé kò bá ìlànà àwọn ara Róòmù mu pé kí a fi ẹnì kan léni lọ́wọ́ láti fi wá ojú rere, kí ẹni tí wọ́n fẹ̀sùn kàn náà tó fojú kojú pẹ̀lú àwọn tó fẹ̀sùn kàn án, kí ó sì láǹfààní láti gbèjà ara rẹ̀ lórí ẹ̀sùn náà.+ 17 Torí náà, nígbà tí wọ́n débí, mi ò fi ọ̀rọ̀ náà falẹ̀, lọ́jọ́ kejì mo jókòó sórí ìjókòó ìdájọ́, mo sì pàṣẹ pé kí wọ́n mú ọkùnrin náà wọlé. 18 Àwọn tó mú ẹ̀sùn wá dìde dúró, àmọ́ wọn ò fi ìkankan nínú ẹ̀sùn ohun burúkú tí mo rò pé ó ṣe kàn án.+ 19 Wọ́n kàn ń ṣe awuyewuye pẹ̀lú rẹ̀ nípa ìjọsìn ọlọ́run àjúbàfún*+ wọn àti nípa ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Jésù, tó ti kú ṣùgbọ́n tí Pọ́ọ̀lù ń tẹnu mọ́ pé ó wà láàyè.+ 20 Nítorí mi ò mọ bí mo ṣe lè yanjú awuyewuye yìí, mo béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ bóyá ó fẹ́ lọ sí Jerúsálẹ́mù, kí a sì dá ẹjọ́ rẹ̀ níbẹ̀ lórí ọ̀ràn yìí.+ 21 Àmọ́ nígbà tí Pọ́ọ̀lù ké gbàjarè pé kí a fi òun sílẹ̀ nínú àhámọ́ títí di ìgbà tí Ẹni Ọlọ́lá* máa ṣèpinnu,+ mo pàṣẹ pé kí a fi í síbẹ̀ títí màá fi rán an lọ sọ́dọ̀ Késárì.”

22 Ágírípà wá sọ fún Fẹ́sítọ́ọ̀sì pé: “Mo fẹ́ gbọ́ ọ̀rọ̀ lẹ́nu ọkùnrin náà fúnra mi.”+ Ó fèsì pé: “Ní ọ̀la, wàá gbọ́ ọ̀rọ̀ lẹ́nu rẹ̀.” 23 Torí náà, lọ́jọ́ kejì, Ágírípà àti Bẹ̀níìsì dé pẹ̀lú ọ̀pọ̀ afẹfẹyẹ̀yẹ̀, wọ́n sì wọnú gbọ̀ngàn àwùjọ pẹ̀lú àwọn ọ̀gágun àti àwọn ọkùnrin jàǹkàn-jàǹkàn ní ìlú náà; nígbà tí Fẹ́sítọ́ọ̀sì pàṣẹ, wọ́n mú Pọ́ọ̀lù wọlé. 24 Fẹ́sítọ́ọ̀sì wá sọ pé: “Ọba Ágírípà àti gbogbo ẹ̀yin tí ẹ wà pẹ̀lú wa, ọkùnrin tí ẹ̀ ń wò yìí ni gbogbo àwọn Júù tó wà ní Jerúsálẹ́mù àti níbí yìí fi ẹjọ́ rẹ̀ sùn mí, tí wọ́n ń kígbe pé kò yẹ kó wà láàyè mọ́.+ 25 Àmọ́ mo rí i pé kò ṣe nǹkan kan tó yẹ fún ikú.+ Torí náà, nígbà tí ọkùnrin yìí fúnra rẹ̀ ké gbàjarè sí Ẹni Ọlọ́lá, mo pinnu pé màá rán an lọ. 26 Ṣùgbọ́n mi ò ní ohun pàtó tí mo lè kọ nípa rẹ̀ sí Olúwa mi. Nítorí náà, mo mú un wá síwájú gbogbo yín, ní pàtàkì síwájú rẹ, Ọba Ágírípà, kí n lè rí nǹkan kọ, lẹ́yìn tí àyẹ̀wò ẹjọ́ rẹ̀ bá ti wáyé. 27 Lójú tèmi, ó dà bíi pé kò bọ́gbọ́n mu láti fi ẹlẹ́wọ̀n kan ránṣẹ́, kí n má sì tọ́ka sí àwọn ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn án.”

26 Ágírípà+ sọ fún Pọ́ọ̀lù pé: “A gbà ọ́ láyè láti rojọ́ ara rẹ.” Nígbà náà, Pọ́ọ̀lù na ọwọ́ rẹ̀, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í gbèjà ara rẹ̀, ó ní:

2 “Lórí gbogbo ohun tí àwọn Júù fẹ̀sùn rẹ̀ kàn mí,+ Ọba Ágírípà, mo ka ara mi sí aláyọ̀ pé iwájú rẹ ni màá ti gbèjà ara mi lónìí yìí, 3 ní pàtàkì, torí pé ọ̀jáfáfá ni ọ́ nínú gbogbo àṣà àti àríyànjiyàn àwọn Júù. Nítorí náà, mo bẹ̀ ọ́ pé kí o fi sùúrù gbọ́rọ̀ mi.

4 “Ní tòótọ́, irú ìgbésí ayé tí mo gbé láti ìgbà èwe mi láàárín àwọn èèyàn* mi àti ní Jerúsálẹ́mù ni gbogbo àwọn Júù mọ̀ dáadáa,+ 5 ìyẹn àwọn tó ti mọ̀ mí tipẹ́tipẹ́, tí wọ́n bá fẹ́, wọ́n lè jẹ́rìí sí i pé ìgbé ayé Farisí ni mo gbé+ ní ìlànà ẹ̀ya ìsìn tí kò gba gbẹ̀rẹ́ rárá,+ ti ọ̀nà ìjọsìn wa. 6 Àmọ́ ní báyìí, torí pé mò ń retí ìlérí tí Ọlọ́run ṣe fún àwọn baba ńlá wa+ ni mo ṣe ń jẹ́jọ́; 7 ìlérí yìí kan náà ni àwọn ẹ̀yà méjìlá (12) wa ń retí pé kó ṣẹ bí wọ́n ṣe ń ṣe iṣẹ́ ìsìn mímọ́ fún un tọ̀sántòru. Ìrètí yìí ló mú kí àwọn Júù fẹ̀sùn kàn mí o,+ Ọba.

8 “Kí nìdí tí ẹ fi kà á sí* ohun tí kò ṣeé gbà gbọ́ láàárín yín pé Ọlọ́run ń jí òkú dìde? 9 Ní tèmi, mo gbà tẹ́lẹ̀ pé ó yẹ kí n gbé ọ̀pọ̀ àtakò dìde sí orúkọ Jésù ará Násárẹ́tì. 10 Ohun tí mo sì ṣe gẹ́lẹ́ ní Jerúsálẹ́mù nìyẹn, ọ̀pọ̀ lára àwọn ẹni mímọ́ ni mo tì mọ́ inú ẹ̀wọ̀n,+ torí mo ti gba àṣẹ lọ́wọ́ àwọn olórí àlùfáà;+ nígbà tí wọ́n sì fẹ́ pa wọ́n, mo dìbò pé kí wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀. 11 Bí mo ṣe ń fìyà jẹ wọ́n léraléra ní gbogbo sínágọ́gù, mo fipá mú wọn láti fi ìgbàgbọ́ wọn sílẹ̀; torí pé inú wọn ń bí mi gidigidi, mo bá a débi pé mo ṣe inúnibíni sí wọn ní àwọn ìlú tó wà lẹ́yìn òde pàápàá.

12 “Ẹnu èyí ni mo wà nígbà tí mò ń rìnrìn àjò lọ sí Damásíkù pẹ̀lú àṣẹ àti agbára látọ̀dọ̀ àwọn olórí àlùfáà, 13 lójú ọ̀nà ní ọ̀sán gangan, ìwọ Ọba, mo rí ìmọ́lẹ̀ kan tó ju ìtànṣán oòrùn, tó kọ mànà láti ọ̀run yí mi ká àti yí àwọn tí a jọ ń rìnrìn àjò ká.+ 14 Nígbà tí gbogbo wa sì ṣubú lulẹ̀, mo gbọ́ ohùn kan tó sọ fún mi lédè Hébérù pé: ‘Sọ́ọ̀lù, Sọ́ọ̀lù, kí ló dé tí ò ń ṣe inúnibíni sí mi? Tí o bá ń tàpá sí ọ̀pá kẹ́sẹ́,* ó máa nira fún ọ.’ 15 Àmọ́ mo sọ pé: ‘Ta ni ọ́, Olúwa?’ Olúwa sì fèsì pé: ‘Èmi ni Jésù, ẹni tí ò ń ṣe inúnibíni sí. 16 Ní báyìí, dìde dúró lórí ẹsẹ̀ rẹ. Ìdí tí mo fi fara hàn ọ́ ni pé, mo fẹ́ yàn ọ́ ṣe ìránṣẹ́ àti ẹlẹ́rìí àwọn ohun tí o ti rí àti àwọn ohun tí màá mú kí o rí nípa mi.+ 17 Màá sì gbà ọ́ lọ́wọ́ àwọn èèyàn yìí àti lọ́wọ́ àwọn orílẹ̀-èdè tí màá rán ọ sí+ 18 láti la ojú wọn,+ láti mú wọn kúrò nínú òkùnkùn+ wá sínú ìmọ́lẹ̀+ àti láti mú wọn kúrò lábẹ́ àṣẹ Sátánì+ wá sọ́dọ̀ Ọlọ́run, kí wọ́n lè rí ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ gbà,+ kí wọ́n sì rí ogún láàárín àwọn tí ìgbàgbọ́ wọn nínú mi ti sọ wọ́n di mímọ́.’

19 “Nítorí náà, Ọba Ágírípà, mi ò ṣàìgbọràn sí ìran àtọ̀runwá náà, 20 àmọ́ mo jẹ́ iṣẹ́ náà fún àwọn tó wà ní Damásíkù+ lákọ̀ọ́kọ́, lẹ́yìn náà fún àwọn tó wà ní Jerúsálẹ́mù + àti fún gbogbo ilẹ̀ Jùdíà àti fún àwọn orílẹ̀-èdè pẹ̀lú, pé kí wọ́n ronú pìwà dà, kí wọ́n sì yíjú sí Ọlọ́run nípa ṣíṣe àwọn iṣẹ́ tó fi ìrònúpìwàdà hàn.+ 21 Ìdí nìyí tí àwọn Júù fi gbá mi mú nínú tẹ́ńpìlì, tí wọ́n sì fẹ́ pa mí.+ 22 Àmọ́ torí pé mo rí ìrànlọ́wọ́ gbà látọ̀dọ̀ Ọlọ́run, mò ń jẹ́rìí nìṣó títí di òní yìí fún ẹni kékeré àti ẹni ńlá, mi ò sì sọ nǹkan kan tó yàtọ̀ sí ohun tí àwọn Wòlíì àti Mósè sọ pé ó máa ṣẹlẹ̀,+ 23 pé Kristi máa jìyà+ àti pé bó ṣe jẹ́ ẹni àkọ́kọ́ tí a máa jí dìde kúrò nínú ikú,+ ó máa kéde ìmọ́lẹ̀ fún àwọn èèyàn yìí àti fún àwọn orílẹ̀-èdè.”+

24 Bí Pọ́ọ̀lù ṣe ń sọ àwọn nǹkan yìí láti gbèjà ara rẹ̀, Fẹ́sítọ́ọ̀sì kígbe pé: “Orí ẹ ti ń dà rú, Pọ́ọ̀lù! Ọ̀pọ̀ ẹ̀kọ́ ti ń dà ẹ́ lórí rú!” 25 Àmọ́ Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Kì í ṣe pé orí mi ń dà rú, Fẹ́sítọ́ọ̀sì Ọlọ́lá Jù Lọ, òótọ́ ọ̀rọ̀ tó mọ́gbọ́n dání ni mò ń sọ. 26 Ká sòótọ́, ọba tí mò ń bá sọ̀rọ̀ ní fàlàlà gan-an mọ̀ nípa àwọn nǹkan yìí dáadáa; ó dá mi lójú pé kò sí ìkankan nínú wọn tí kò mọ̀ nípa rẹ̀, torí kò sí ìkankan nínú wọn tó ṣẹlẹ̀ ní kọ̀rọ̀.+ 27 Ọba Ágírípà, ṣé o gba àwọn Wòlíì gbọ́? Mo mọ̀ pé o gbà wọ́n gbọ́.” 28 Àmọ́ Ágírípà sọ fún Pọ́ọ̀lù pé: “Ní àkókò díẹ̀ sí i, wàá sọ mí* di Kristẹni.” 29 Ni Pọ́ọ̀lù bá sọ pé: “Ohun tí mò ń bẹ Ọlọ́run ni pé ì báà jẹ́ ní àkókò kúkúrú tàbí ní àkókò gígùn, kó má ṣe jẹ́ ìwọ nìkan, ṣùgbọ́n kí gbogbo àwọn tó ń gbọ́rọ̀ mi lónìí náà dà bíi tèmi, àmọ́ láìsí nínú ìdè ẹ̀wọ̀n yìí.”

30 Lẹ́yìn náà, ọba dìde, gómìnà àti Bẹ̀níìsì pẹ̀lú àwọn èèyàn tí wọ́n jọ jókòó sì dìde. 31 Àmọ́ bí wọ́n ṣe ń fi ibẹ̀ sílẹ̀, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í bá ara wọn sọ̀rọ̀, pé: “Ọkùnrin yìí ò ṣe nǹkan kan tó yẹ fún ikú tàbí ìdè ẹ̀wọ̀n.”+ 32 Ágírípà wá sọ fún Fẹ́sítọ́ọ̀sì pé: “À bá dá ọkùnrin yìí sílẹ̀ ká ní kò ké gbàjarè sí Késárì.”+

27 Ní báyìí tí wọ́n ti pinnu pé kí a wọkọ̀ òkun lọ sí Ítálì,+ wọ́n fa Pọ́ọ̀lù àti àwọn ẹlẹ́wọ̀n míì lé ọwọ́ ọ̀gá àwọn ọmọ ogun kan tó ń jẹ́ Júlíọ́sì, orúkọ àwùjọ ọmọ ogun rẹ̀ ni Ọ̀gọ́sítọ́sì. 2 A wọ ọkọ̀ òkun kan láti Adiramítíúmù tó fẹ́ lọ sí àwọn èbúté tó wà ní etíkun ìpínlẹ̀ Éṣíà, ọkọ̀ náà sì gbéra; Àrísítákọ́sì+ ará Makedóníà láti Tẹsalóníkà wà pẹ̀lú wa. 3 Lọ́jọ́ kejì, a gúnlẹ̀ sí Sídónì, Júlíọ́sì ṣojú rere* sí Pọ́ọ̀lù, ó sì gbà á láyè láti lọ sọ́dọ̀ àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀, kí wọ́n sì ṣìkẹ́ rẹ̀.

4 Nígbà tí a wọkọ̀ òkun kúrò níbẹ̀, a gba tòsí Sápírọ́sì, kí a lè bọ́ lọ́wọ́ ẹ̀fúùfù tó dojú kọ wá. 5 Lẹ́yìn náà, a gba ojú òkun kọjá Sìlíṣíà àti Panfílíà, a sì gúnlẹ̀ sí èbúté ní Máírà ní Líkíà. 6 Ibẹ̀ ni ọ̀gá ọmọ ogun náà ti rí ọkọ̀ òkun kan tó ń bọ̀ láti Alẹkisáńdíríà, tó ń lọ sí Ítálì, ó sì mú wa wọ̀ ọ́. 7 Lẹ́yìn ọjọ́ díẹ̀ tí a ti rọra ń tukọ̀ bọ̀, a dé Kínídọ́sì tipátipá. Nítorí pé ẹ̀fúùfù kò jẹ́ kí a lọ tààrà, a fi Sálímónè sílẹ̀ gba tòsí Kírétè. 8 Bí a ṣe ń tukọ̀ lọ ní etíkun náà tipátipá, a dé ibì kan tí wọ́n ń pè ní Èbúté Rere, tó wà nítòsí ìlú Láséà.

9 Àkókò púpọ̀ ti kọjá, ó sì ti wá léwu láti tukọ̀ torí ààwẹ̀ Ọjọ́ Ètùtù+ pàápàá ti kọjá, nítorí náà Pọ́ọ̀lù dá àbá kan 10 fún wọn pé: “Ẹ̀yin èèyàn, mo ri í pé ìrìn àjò yìí máa yọrí sí òfò àti àdánù ńlá, kì í ṣe ẹrù àti ọkọ̀ òkun yìí nìkan ló máa kàn, ó máa kan ẹ̀mí* wa náà.” 11 Àmọ́, ohun tí atukọ̀ àti ọlọ́kọ̀ sọ ni ọ̀gá ọmọ ogun fara mọ́, kò fara mọ́ ohun tí Pọ́ọ̀lù sọ. 12 Torí pé kò dẹrùn láti lo ìgbà òtútù ní èbúté náà, àwọn tó pọ̀ jù dámọ̀ràn pé ká tukọ̀ kúrò níbẹ̀, wọ́n ń wò ó bóyá a máa lè dé Fóníìsì ká lè lo ìgbà òtútù níbẹ̀, ibẹ̀ jẹ́ èbúté kan ní Kírétè, ó dojú kọ àríwá ìlà oòrùn àti gúúsù ìlà oòrùn.

13 Nígbà tí atẹ́gùn gúúsù fẹ́ yẹ́ẹ́, wọ́n rò pé ọwọ́ wọn ti tẹ ohun tí wọ́n ń fẹ́, wọ́n bá fa ìdákọ̀ró sókè, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í tukọ̀ lọ lẹ́gbẹ̀ẹ́ Kírétè nítòsí èbúté. 14 Àmọ́, lẹ́yìn àkókò díẹ̀, ìjì líle tí wọ́n ń pè ní Yúrákúílò* rọ́ lù ú. 15 Bí ó ṣe fipá gba ọkọ̀ òkun náà, tí a kò sì lè dorí rẹ̀ kọ ìjì náà, a gba kámú, ìjì náà sì ń gbá wa lọ. 16 Lẹ́yìn náà, a sáré wọ erékùṣù kékeré kan tí wọ́n ń pè ní Káúdà, síbẹ̀ agbára káká la fi lè ṣèkáwọ́ ọkọ̀ ìgbájá* tó wà ní ẹ̀yìn ọkọ̀. 17 Àmọ́ lẹ́yìn tí wọ́n fà á sókè sínú ọkọ̀, wọ́n fi àwọn nǹkan di ẹ̀gbẹ́ ọkọ̀ òkun náà pọ̀ lábẹ́, torí pé ẹ̀rù ń bà wọ́n kí ọkọ̀ náà má lọ fàyà sọlẹ̀ ní Sítísì,* wọ́n ta ìgbòkun, ìjì náà sì ń gbé wa lọ. 18 Nítorí pé ìjì líle náà ń fi agbára gbá wa síwá-sẹ́yìn, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í mú ọkọ̀ òkun náà fúyẹ́ ní ọjọ́ tó tẹ̀ lé e. 19 Ní ọjọ́ kẹta, wọ́n fi ọwọ́ ara wọn da àwọn ohun èlò inú ọkọ̀ òkun náà nù.

20 Nígbà tí oòrùn tàbí ìràwọ̀ kò yọ fún ọ̀pọ̀ ọjọ́, tí ìjì líle* sì ń bá wa fà á, a bẹ̀rẹ̀ sí í wò ó pé bóyá la fi lè là á já. 21 Lẹ́yìn ọ̀pọ̀lọpọ̀ àkókò tí wọ́n ti lò láìjẹun, Pọ́ọ̀lù dìde dúró láàárín wọn, ó sì sọ pé: “Ẹ̀yin èèyàn, ó yẹ kí ẹ ti gba ìmọ̀ràn mi, kí ẹ má sì ṣíkọ̀ sójú òkun láti Kírétè, ẹ̀ bá má ti rí òfò àti àdánù yìí.+ 22 Síbẹ̀, ní báyìí, mo rọ̀ yín pé kí ẹ mọ́kàn le, torí kò sí ìkankan* lára yín tó máa ṣègbé, àyàfi ọkọ̀ òkun yìí. 23 Ní òru yìí, áńgẹ́lì+ Ọlọ́run tí mo jẹ́ tirẹ̀, tí mo sì ń ṣe iṣẹ́ ìsìn mímọ́ fún dúró lẹ́gbẹ̀ẹ́ mi, 24 ó sì sọ pé: ‘Má bẹ̀rù, Pọ́ọ̀lù. Wàá dúró níwájú Késárì,+ sì wò ó! Ọlọ́run ti fún ọ ní gbogbo àwọn tí ẹ jọ wà nínú ọkọ̀.’ 25 Nítorí náà, ẹ̀yin èèyàn, ẹ mọ́kàn le, torí mo gba Ọlọ́run gbọ́ pé bó ṣe sọ fún mi ló máa rí. 26 Àmọ́ ṣá o, ọkọ̀ wa máa lọ fàyà sọlẹ̀ sí èbúté ní erékùṣù kan.”+

27 Nígbà tó di òru kẹrìnlá, tí ìjì sì ń bì wá síwá-sẹ́yìn lórí Òkun Ádíríà, ní ọ̀gànjọ́ òru, àwọn òṣìṣẹ́ ọkọ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í fura pé wọ́n ti ń sún mọ́ ilẹ̀ kan. 28 Wọ́n wọn jíjìn omi náà wò, wọ́n sì rí i pé ó jẹ́ ogún (20) fátọ́ọ̀mù,* torí náà, wọ́n rìn síwájú díẹ̀, wọ́n tún wọn jíjìn omi náà, wọ́n sì rí i pé ó jẹ́ fátọ́ọ̀mù mẹ́ẹ̀ẹ́dógún (15).* 29 Torí pé wọ́n ń bẹ̀rù kí a má lọ fàyà sọ àpáta, wọ́n ju ìdákọ̀ró mẹ́rin sínú omi láti ẹ̀yìn ọkọ̀, wọ́n sì ń retí pé kí ilẹ̀ mọ́. 30 Àmọ́ nígbà tí àwọn òṣìṣẹ́ ọkọ̀ fẹ́ sá kúrò nínú ọkọ̀ òkun náà, tí wọ́n sì ń rọ ọkọ̀ ìgbájá sílẹ̀ sínú òkun, bíi pé ṣe ni wọ́n fẹ́ rọ àwọn ìdákọ̀ró sísàlẹ̀ láti iwájú ọkọ̀, 31 Pọ́ọ̀lù sọ fún ọ̀gá àwọn ọmọ ogun àti àwọn ọmọ ogun pé: “Láìjẹ́ pé àwọn èèyàn yìí dúró sínú ọkọ̀ òkun yìí, ẹ ò lè yè bọ́ o.”+ 32 Ni àwọn ọmọ ogun bá gé okùn ọkọ̀ ìgbájá náà, ó sì já bọ́.

33 Nígbà tí ilẹ̀ ti fẹ́rẹ̀ẹ́ mọ́, Pọ́ọ̀lù gba gbogbo wọn níyànjú pé kí wọ́n jẹun, ó ní: “Òní ló pé ọjọ́ kẹrìnlá tí ẹ ti ń wọ̀nà lójú méjèèjì, tí ẹ ò sì jẹ nǹkan kan rárá. 34 Nítorí náà, mo rọ̀ yín pé kí ẹ jẹun; torí kó má bàa sí ewu fún yín, nítorí kò sí ìkankan nínú irun orí ẹnì kọ̀ọ̀kan yín tó máa ṣègbé.” 35 Lẹ́yìn tó sọ ọ̀rọ̀ yìí, ó mú búrẹ́dì, ó dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run níwájú gbogbo wọn, ó bù ú, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í jẹun. 36 Torí náà, gbogbo wọn mọ́kàn le, àwọn náà sì bẹ̀rẹ̀ sí í jẹun. 37 Gbogbo àwa* tí a wà nínú ọkọ̀ òkun náà jẹ́ igba ó lé mẹ́rìndínlọ́gọ́rin (276). 38 Nígbà tí wọ́n ti jẹun yó, wọ́n gbé àwọn àlìkámà* tó wà nínú ọkọ̀ náà jù sínú òkun kí ọkọ̀ náà lè fúyẹ́.+

39 Nígbà tí ojú mọ́, wọn ò mọ ojú ilẹ̀,+ àmọ́ wọ́n rí ibì kan tí ilẹ̀ wà ní etíkun, wọ́n sì pinnu pé àwọn á mú kí ọkọ̀ òkun náà gúnlẹ̀ síbẹ̀ tó bá ṣeé ṣe. 40 Torí náà, wọ́n gé àwọn ìdákọ̀ró kúrò, wọ́n sì jẹ́ kí wọ́n já bọ́ sínú òkun, ní àkókò kan náà, wọ́n tú àwọn okùn tí wọ́n fi so àwọn àjẹ̀ ìtọ́kọ̀; lẹ́yìn tí wọ́n ta ìgbòkun iwájú ọkọ̀ sínú afẹ́fẹ́, wọ́n dorí kọ etíkun náà. 41 Nígbà tí wọ́n fàyà gbá òkìtì kan lábẹ́ omi, tí omi n gba ẹ̀gbẹ́ rẹ̀ méjèèjì kọjá, ọkọ̀ wọn fàyà sọlẹ̀, iwájú ọkọ̀ fẹnu gúnlẹ̀, kò sì lè lọ mọ́, ni ìgbì bá bẹ̀rẹ̀ sí í fọ́ ìdí ọkọ̀ náà sí wẹ́wẹ́.+ 42 Àwọn ọmọ ogun wá fẹ́ pa àwọn ẹlẹ́wọ̀n kí ìkankan nínú wọn má bàa lúwẹ̀ẹ́ sá lọ. 43 Àmọ́ ọ̀gá àwọn ọmọ ogun pinnu láti mú Pọ́ọ̀lù gúnlẹ̀ láìséwu, kò sì jẹ́ kí wọ́n ṣe ohun tí wọ́n fẹ́. Ó pàṣẹ fún àwọn tó mọ̀ ọ́n wẹ̀ pé kí wọ́n bẹ́ sínú òkun, kí wọ́n sì kọ́kọ́ lọ sórí ilẹ̀, 44 kí àwọn tó kù wá tẹ̀ lé wọn, àwọn kan lórí pátákó, àwọn míì lórí àwọn àfọ́kù ara ọkọ̀ òkun náà. Nítorí náà, gbogbo wa dórí ilẹ̀ láìséwu.+

28 Lẹ́yìn tí a gúnlẹ̀ ní àlàáfíà, a gbọ́ pé Málítà ni wọ́n ń pe erékùṣù náà.+ 2 Àwọn tó ń sọ èdè àjèjì* ṣe inú rere àrà ọ̀tọ̀* sí wa. Wọ́n dá iná, wọ́n sì gba gbogbo wa tọwọ́tẹsẹ̀ nítorí òjò tó ń rọ̀ àti nítorí òtútù tó mú. 3 Àmọ́ nígbà tí Pọ́ọ̀lù kó igi jọ, tó sì kó o sórí iná, paramọ́lẹ̀ kan jáde nítorí ooru, ó sì wé mọ́ ọn lọ́wọ́. 4 Nígbà tí àwọn tó ń sọ èdè àjèjì tajú kán rí ejò olóró tó rọ̀ dirodiro ní ọwọ́ rẹ̀, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í sọ fún ara wọn pé: “Ó dájú pé apààyàn ni ọkùnrin yìí, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó gúnlẹ̀ ní àlàáfíà láti orí òkun, Ìdájọ́ Òdodo* kò jẹ́ kó máa wà láàyè nìṣó.” 5 Àmọ́, ó gbọn ejò náà dà nù sínú iná, nǹkan kan ò sì ṣe é. 6 Síbẹ̀, wọ́n ń retí pé kí ara rẹ̀ wú tàbí pé lójijì, kó ṣubú lulẹ̀, kó sì kú. Nígbà tí wọ́n dúró títí, tí wọ́n sì rí i pé nǹkan kan ò ṣe é, wọ́n yí èrò wọn pa dà, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í sọ pé ọlọ́run kan ni.

7 Ní àdúgbò ibẹ̀, àwọn ilẹ̀ kan wà tó jẹ́ ti olórí erékùṣù náà, Púbílọ́sì ni orúkọ rẹ̀, ó gbà wá tọwọ́tẹsẹ̀, ó sì ṣe wá lálejò fún ọjọ́ mẹ́ta. 8 Ó ṣẹlẹ̀ pé bàbá Púbílọ́sì wà lórí ìdùbúlẹ̀ àìsàn, ibà àti ìgbẹ́ ọ̀rìn ń yọ ọ́ lẹ́nu, Pọ́ọ̀lù wá wọlé lọ bá a, ó sì gbàdúrà, ó gbé ọwọ́ lé e, ó sì mú un lára dá.+ 9 Lẹ́yìn tí èyí ṣẹlẹ̀, ìyókù àwọn èèyàn erékùṣù náà tó ń ṣàìsàn bẹ̀rẹ̀ sí í wá sọ́dọ̀ rẹ̀, wọ́n sì ń rí ìwòsàn.+ 10 Wọ́n tún fi ọ̀pọ̀ ẹ̀bùn yẹ́ wa sí, nígbà tí a sì fẹ́ lọ wọkọ̀, wọ́n di gbogbo ohun tí a nílò fún wa.

11 Oṣù mẹ́ta lẹ́yìn náà, a wọkọ̀ òkun kan tí wọ́n kọ “Àwọn Ọmọ Súúsì” sára ère iwájú orí rẹ̀. Alẹkisáńdíríà ni ọkọ̀ òkun náà ti wá, ó sì ti lo ìgbà òtútù ní erékùṣù náà. 12 A gúnlẹ̀ sí èbúté Sírákúsì, a sì lo ọjọ́ mẹ́ta níbẹ̀; 13 látibẹ̀, a tẹ̀ síwájú, a sì dé Régíómù. Ọjọ́ kan lẹ́yìn náà, ẹ̀fúùfù gúúsù kan bẹ̀rẹ̀, síbẹ̀ náà, a dé Pútéólì lọ́jọ́ kejì. 14 A rí àwọn ará níbẹ̀, wọ́n sì rọ̀ wá pé ká lo ọjọ́ méje lọ́dọ̀ àwọn, lẹ́yìn náà a forí lé Róòmù. 15 Nígbà tí àwọn ará gbọ́ ìròyìn nípa wa, wọ́n wá láti ibẹ̀, títí dé iyànníyàn Ibi Ọjà Ápíọ́sì àti Ilé Èrò Mẹ́ta láti wá pàdé wa. Nígbà tí Pọ́ọ̀lù tajú kán rí wọn, ó dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run, ó sì mọ́kàn le.+ 16 Níkẹyìn, a wọ Róòmù, wọ́n sì gba Pọ́ọ̀lù láyè kó máa gbé láyè ara rẹ̀ pẹ̀lú ọmọ ogun tó ń ṣọ́ ọ.

17 Àmọ́, ọjọ́ mẹ́ta lẹ́yìn náà, Pọ́ọ̀lù pe àwọn sàràkí-sàràkí jọ lára àwọn Júù. Nígbà tí wọ́n pé jọ, ó sọ fún wọn pé: “Ẹ̀yin èèyàn, ẹ̀yin ará, bó tilẹ̀ jẹ́ pé mi ò ṣe ohunkóhun tó lòdì sí àwọn èèyàn tàbí sí àṣà àwọn baba ńlá wa,+ síbẹ̀ wọ́n fà mí lé ọwọ́ àwọn ará Róòmù ní ẹlẹ́wọ̀n láti Jerúsálẹ́mù.+ 18 Lẹ́yìn tí wọ́n ṣe àyẹ̀wò,+ wọ́n fẹ́ dá mi sílẹ̀, nítorí kò sí ìdí kankan tó fi yẹ kí wọ́n pa mí.+ 19 Àmọ́ nígbà tí àwọn Júù fárí gá, ó di dandan fún mi láti ké gbàjarè sí Késárì,+ ṣùgbọ́n kì í ṣe torí pé mo ní ẹ̀sùn tí mo fẹ́ fi kan orílẹ̀-èdè mi. 20 Ìdí nìyí tí mo fi ní kí n pè yín kí n lè bá yín sọ̀rọ̀, torí pé, nítorí ìrètí Ísírẹ́lì ni ẹ̀wọ̀n yìí ṣe yí mi ká.”+ 21 Wọ́n sọ fún un pé: “A ò tíì gba lẹ́tà kankan nípa rẹ láti Jùdíà, bẹ́ẹ̀ ni kò sí ìkankan lára àwọn ará tó wá láti ibẹ̀ tó ròyìn tàbí tó sọ ohun burúkú nípa rẹ. 22 Àmọ́, a rí i pé á dáa ká gbọ́rọ̀ lẹ́nu rẹ, ká lè mọ ohun tó wà lọ́kàn rẹ, torí a mọ̀ lóòótọ́ pé, tó bá dọ̀rọ̀ ẹ̀ya ìsìn yìí,+ ibi gbogbo ni wọ́n ti ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ láìdáa.”+

23 Wọ́n wá ṣètò ọjọ́ kan láti wá bá a, wọ́n sì wá sọ́dọ̀ rẹ̀ ní ibi tó ń gbé, kódà àwọn tó wá pọ̀ ju ti ìṣáájú lọ. Láti àárọ̀ ṣúlẹ̀, ó ṣàlàyé ọ̀ràn náà fún wọn bí ó ṣe ń jẹ́rìí kúnnákúnná nípa Ìjọba Ọlọ́run, kó lè yí èrò tí wọ́n ní nípa Jésù pa dà+ nípasẹ̀ Òfin Mósè+ àti ìwé àwọn Wòlíì.+ 24 Àwọn kan bẹ̀rẹ̀ sí í gba ohun tó sọ gbọ́; àmọ́ àwọn míì ò gbà á gbọ́. 25 Tóò, nígbà tí èrò wọn ò ṣọ̀kan, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í fi ibẹ̀ sílẹ̀, Pọ́ọ̀lù wá sọ ọ̀rọ̀ kan, ó ní:

“Ẹ̀mí mímọ́ sọ̀rọ̀ lọ́nà tó ṣe wẹ́kú nípasẹ̀ wòlíì Àìsáyà fún àwọn baba ńlá yín, 26 pé, ‘Lọ sọ fún àwọn èèyàn yìí pé: “Ó dájú pé ẹ ó gbọ́, àmọ́ kò ní yé yín rárá; ó dájú pé ẹ ó wò, àmọ́ ẹ ò ní rí nǹkan kan.+ 27 Nítorí ọkàn àwọn èèyàn yìí ti yigbì, wọ́n ti fi etí wọn gbọ́ àmọ́ wọn ò dáhùn, wọ́n ti di ojú wọn, kí wọ́n má bàa fi ojú wọn ríran láé, kí wọ́n má sì fi etí wọn gbọ́, kó má sì yé wọn nínú ọkàn wọn, kí wọ́n lè yí pa dà, kí n sì mú wọn lára dá.”’+ 28 Torí náà, ẹ jẹ́ kó yé yín pé, ìgbàlà yìí tó wá látọ̀dọ̀ Ọlọ́run ni a ti kéde fún àwọn orílẹ̀-èdè;+ ó dájú pé wọ́n á fetí sí i.”+ 29 * ——

30 Torí náà, ó lo odindi ọdún méjì ní ilé tí òun fúnra rẹ̀ gbà,+ ó sì máa ń gba gbogbo àwọn tó bá wá sọ́dọ̀ rẹ̀ tọwọ́tẹsẹ̀, 31 ó ń wàásù Ìjọba Ọlọ́run fún wọn, ó sì ń kọ́ wọn nípa Jésù Kristi Olúwa ní fàlàlà,*+ láìsí ìdíwọ́.

Tàbí “abẹ́ àṣẹ.”

Tàbí “dé ìkángun ayé.”

Tàbí “èrò.”

Tàbí “ó bẹ́ ní àárín.”

Ní Grk., “fi ń wọlé, tó sì ń jáde.”

Wo Àfikún A5.

Tàbí “kà á kún,” ìyẹn ni pé, ojú tí wọ́n fi ń wo àwọn àpọ́sítélì mọ́kànlá tó kù ni wọ́n fi ń wò ó.

Tàbí “fi oríṣiríṣi ahọ́n sọ̀rọ̀.”

Tàbí “èdè àbínibí.”

Ìyẹn, àwọn tó gba ẹ̀sìn Júù. Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.

Tàbí “wáìnì tuntun.”

Ìyẹn, nǹkan bí aago mẹ́sàn-án àárọ̀.

Ní Grk., “ẹran ara.”

Tàbí “àwọn àmì.”

Wo Àfikún A5.

Wo Àfikún A5.

Tàbí “àwọn àmì.”

Tàbí “ìfẹ́.”

Tàbí “mọ́ òpó igi.” Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.

Tàbí kó jẹ́, “okùn.”

Wo Àfikún A5.

Ní Grk., “Ẹran ara mi á.”

Tàbí “ọkàn mi.”

Tàbí “Hédíìsì,” ìyẹn ibojì aráyé. Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.

Ní Grk., “ẹnì kan látinú èso abẹ́ rẹ̀.”

Tàbí “Hédíìsì,” ìyẹn ibojì aráyé. Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.

Tàbí “kò jẹrà.”

Wo Àfikún A5.

Tàbí “mọ́ òpó igi.” Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.

Wo Àfikún A5.

Tàbí “ọkàn.”

Tàbí “wọ́n ń fún ara wọn ní nǹkan.”

Tàbí “ọkàn.”

Tàbí “àmì.”

Wo Àfikún A5.

Ìyẹn, nǹkan bí aago mẹ́ta ọ̀sán.

Tàbí “Ìloro.”

Ní Grk., “láti ojú Jèhófà.” Wo Àfikún A5.

Wo Àfikún A5.

Tàbí “ọkàn.”

Ní Grk., “èso.”

Tàbí “àjíǹde kúrò nínú ikú nípasẹ̀ ọ̀ràn Jésù.”

Tàbí “mú wọn.”

Tàbí “mọ́ òpó igi.” Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.

Ní Grk., “olórí igun.”

Tàbí “bí Pétérù àti Jòhánù ṣe fi ìgboyà sọ̀rọ̀.”

Tàbí “mọ̀wé,” ìyẹn ni pé wọn ò lọ sí ilé ẹ̀kọ́ àwọn rábì; kò túmọ̀ sí pé wọn ò lè kàwé.

Tàbí “àmì.”

Wo Àfikún A5.

Tàbí “Kristi.”

Wo Àfikún A5.

Tàbí “àwọn àmì.”

Tàbí “tí wọ́n ti gbàdúrà taratara.”

Ní Grk., “ọkàn.” Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.

Wo Àfikún A5.

Tàbí “àwọn àmì.”

Tàbí “Ìloro.”

Tàbí “wọ́n jowú.”

Tàbí “mú àwọn àpọ́sítélì.”

Wo Àfikún A5.

Tàbí “igi.”

Tàbí “ó dùn wọ́n wọra.”

Tàbí “wọ́n lù wọ́n.”

Ní Grk., “Kò dùn mọ́ wa nínú láti.”

Tàbí “àwọn ọkùnrin méje tí wọ́n sọ̀rọ̀ wọn dáadáa.”

Ìyẹn, ẹni tó gba ẹ̀sìn Júù. Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.

Tàbí “ṣègbọràn sí.”

Tàbí “àwọn àmì.”

Ní Grk., “èso.”

Ní Grk., “èso.”

Tàbí “pọ́n wọn lójú.”

Tàbí “ìkọlà.”

Tàbí “kọlà fún un.”

Tàbí kó jẹ́, “ṣe bákan náà sí.”

Tàbí “àwọn baba ńlá.”

Tàbí “ọkà.”

Tàbí “ọkàn náà.”

Tàbí “ó rẹwà lójú Ọlọ́run.”

Tàbí “tọ́ ọ.”

Tàbí “gbé e síta.”

Tàbí “pinnu.”

Tàbí “ṣèbẹ̀wò sọ́dọ̀.”

Wo Àfikún A5.

Wo Àfikún A5.

Tàbí “àwọn àmì.”

Wo Àfikún A5.

Tàbí “aláìdádọ̀dọ́.”

Tàbí “ó dùn wọ́n wọra.”

Wo Àfikún A5.

Tàbí kó jẹ́, “ìlú kan ní.”

Wo Àfikún A5.

Ní Grk., “òróòro ìkorò.”

Wo Àfikún A5.

Wo Àfikún A5.

Wo Àfikún A5.

Tàbí “òṣìṣẹ́ ààfin.”

Ní Grk., “mọ.”

Wo Àfikún A3.

Wo Àfikún A5.

Ní Grk., “de; fi gbogbo àwọn tó ń ké pe orúkọ rẹ sínú ìdè.”

Ní Grk., “mú wọn ní dídè.”

Ní Grk., “ó ń wọlé wọ̀de.”

Wo Àfikún A5.

Dọ́káàsì jẹ́ orúkọ Gíríìkì, Tàbítà jẹ́ orúkọ Árámáíkì, orúkọ méjèèjì túmọ̀ sí “Egbin.”

Tàbí “ẹ̀wù àwọ̀lékè.”

Tàbí “balógun ọ̀rún,” tó ń darí 100 ọmọ ogun.

Tàbí “àwùjọ ọmọ ogun,” ẹgbẹ́ ọmọ ogun Róòmù tó ní 600 ọmọ ogun.

Ìyẹn, nǹkan bí aago mẹ́ta ọ̀sán.

Tàbí “Wọ́n ń ṣe ọkùnrin yìí lálejò.”

Ìyẹn, nǹkan bí aago méjìlá ọ̀sán.

Ní Grk., “oríṣi ohun èlò kan.”

Tàbí “àwọn ohun tó ń rákò.”

Ní Grk., “ohun èlò náà.”

Tàbí “forí balẹ̀.”

Ìyẹn, nǹkan bí aago mẹ́ta ọ̀sán.

Wo Àfikún A5.

Tàbí “igi.”

Tàbí “ó sì jẹ́ kó ṣeé fojú rí.”

Tàbí “àwọn olóòótọ́.”

Tàbí “kọlà.”

Ní Grk., “fi ahọ́n sọ̀rọ̀.”

Tàbí “ìkọlà.”

Tàbí “bá a jiyàn.”

Tàbí “kọlà.”

Ní Grk., “oríṣi ohun èlò.”

Tàbí “àwọn ohun tó ń rákò.”

Tàbí “dènà Ọlọ́run?”

Ní Grk., “wọ́n dákẹ́.”

Wo Àfikún A5.

Tàbí “ìpèsè adínṣòrokù.”

Tàbí “mú un wá jẹ́jọ́ níwájú.”

Wo Àfikún A5.

Tàbí “Di ara rẹ lámùrè.”

Wo Àfikún A5.

Wo Àfikún A5.

Tàbí “Ìjà ń gùn ún.”

Ní Grk., “bójú tó yàrá ọba.”

Wo Àfikún A5.

Tàbí “àwọn kòkòrò mùkúlú.”

Wo Àfikún A5.

Wo Àfikún A5.

Tàbí “olùrànlọ́wọ́.”

Gómìnà ìjọba Róòmù tó ń ṣàkóso ìpínlẹ̀. Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.

Wo Àfikún A5.

Wo Àfikún A5.

Wo Àfikún A5.

Ní Grk., “ọwọ́ tó ròkè.”

Ní Grk., “èso.”

Tàbí “igi.”

Tàbí “ibojì ìrántí.”

Tàbí “ṣeé gbíyè lé; ṣeé gbára lé.”

Tàbí “ṣe ìfẹ́.”

Ìyẹn, àwọn tó gba ẹ̀sìn Júù. Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.

Wo Àfikún A5.

Tàbí “wọ́n jowú.”

Wo Àfikún A5.

Wo Àfikún A5.

Wo Àfikún A5.

Tàbí “ọkàn àwọn èèyàn.”

Wo Àfikún A5.

Tàbí “àwọn àmì.”

Tàbí “òdòdó àsokọ́ra.”

Tàbí “ọkàn àwọn ọmọ ẹ̀yìn.”

Wo Àfikún A5.

Tàbí “kọlà.”

Tàbí “awuyewuye.”

Tàbí “kọ wọ́n nílà.”

Tàbí “awuyewuye.”

Tàbí “àwọn àmì.”

Tàbí “àtíbàbà; ilé.”

Wo Àfikún A5.

Wo Àfikún A5.

Tàbí “èrò.”

Lédè Gíríìkì, por·neiʹa. Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.

Tàbí “ohun tí wọ́n pa láìro ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ dà nù.”

Tàbí “ọkàn yín.”

Tàbí “ọkàn.”

Tàbí “ohun tí wọ́n pa láìro ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ dà nù.”

Lédè Gíríìkì, por·neiʹa. Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.

Tàbí “Ó dìgbà o.”

Wo Àfikún A3.

Wo Àfikún A5.

Tàbí kó jẹ́., “Ní gbogbo ọ̀nà.”

Wo Àfikún A5.

Wo Àfikún A5.

Tàbí “kọ ọ́ nílà.”

Tàbí “gba inú.”

Wo Àfikún A5.

Wo Àfikún A5.

Tàbí “iṣẹ́ sísọtẹ́lẹ̀.”

Wo Àfikún A5.

Tàbí “láìgbọ́ ẹjọ́ wa.”

Tàbí “dá wàhálà sílẹ̀ ní ilẹ̀ ayé tí à ń gbé.”

Tàbí “gba owó ìtúsílẹ̀.”

Tàbí “ṣèbẹ̀wò síbẹ̀.”

Tàbí “ẹ ní ẹ̀mí ìsìn ju àwọn yòókù lọ.”

Tàbí “jọ́sìn.”

Tàbí “àtọmọdọ́mọ.”

Tàbí “àtọmọdọ́mọ.”

Tàbí “Ó máa ń bá wọn fèròwérò.”

Ìyẹn, sínágọ́gù.

Gómìnà ìjọba Róòmù tó ń ṣàkóso ìpínlẹ̀. Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.

Wo Àfikún A5.

Ó jọ pé, sí Jerúsálẹ́mù.

Tàbí “ti kẹ́kọ̀ọ́ nípasẹ̀ ọ̀rọ̀ ẹnu.”

Wo Àfikún A5.

Tàbí “sé ọkàn wọn le, tí wọn ò gbà á gbọ́.”

Tàbí “aṣọ àwọ̀lékè.”

Wo Àfikún A5.

Gómìnà ìjọba Róòmù tó ń ṣàkóso ìpínlẹ̀. Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.

Tàbí “wíńdò.”

Tàbí “ọkàn rẹ̀ wà nínú rẹ̀.”

Ní Grk., “ó bu búrẹ́dì.”

Tàbí “ìrẹ̀lẹ̀ ọkàn.”

Tàbí “ohun tó máa ṣe yín láǹfààní.”

Ní Grk., “ẹ̀mí ti dè mí.”

Tàbí “ọkàn.”

Tàbí “tó ṣeyebíye.”

Tàbí “gbogbo ohun tí Ọlọ́run ní lọ́kàn.”

Ní Grk., “rọ̀ mọ́ ọrùn Pọ́ọ̀lù.”

Tàbí “lọ́nà jẹ̀lẹ́ńkẹ́.”

Tàbí “apá ibi tí èbúté wà.”

Ní Grk., “tí wọ́n jẹ́ wúńdíá.”

Tàbí “kó àárẹ̀ bá ọkàn mi?”

Ní Grk., “a dákẹ́.”

Wo Àfikún A5.

Tàbí “kọlà fún.”

Tàbí “ohun tí wọ́n pa láìro ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ dà nù.”

Lédè Gíríìkì, por·neiʹa. Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.

Tàbí “tí kò fara sin.”

Ní Grk., “gba ẹ̀kọ́ lẹ́gbẹ̀ẹ́ ẹsẹ̀.”

Tàbí “ọmọ ìbílẹ̀ Róòmù.”

Tàbí “tí wọn ò tíì gbọ́ ẹjọ́ rẹ̀?”

Tàbí “kéde gbogbo rẹ̀ ní gbangba.”

Tàbí “A ti búra.”

Tàbí “ìbúra.”

Ìyẹn, nǹkan bí aago mẹ́sàn-án alẹ́.

Tàbí “ibùgbé.”

Tàbí “agbẹjọ́rò kan.”

Tàbí “oníwàhálà.” Ní Grk., “àjàkálẹ̀ àrùn.”

Wo Àfikún A3.

Tàbí “wà láìlábààwọ́n.”

Ní Grk., “wọ́n béèrè ojú rere lòdì sí i.”

Tàbí “ẹ̀sìn.”

Orúkọ oyè olú ọba Róòmù.

Tàbí “orílẹ̀-èdè.”

Ní Grk., “ṣèdájọ́ pé ó jẹ́.”

Ọ̀pá kẹ́sẹ́ jẹ́ ọ̀pá olórí ṣóńṣó tí wọ́n fi ń da ẹran.

Ní Grk., “yí mi lérò pa dà.”

Tàbí “ṣe dáadáa.”

Tàbí “ọkàn.”

Ìyẹn, ẹ̀fúùfù àríwá ìlà oòrùn kan.

Ọkọ̀ ojú omi kékeré tí wọ́n fi ń gbẹ̀mí là.

Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.

Ní Grk., “tí kì í ṣe kékeré.”

Tàbí “ọkàn kan.”

Nǹkan bíi mítà 36 (ẹsẹ̀ bàtà 120). Wo Àfikún B14.

Nǹkan bíi mítà 27 (ẹsẹ̀ bàtà 90). Wo Àfikún B14.

Tàbí “àwa ọkàn.”

Tàbí “wíìtì.”

Tàbí “Àwọn tó ń gbé ibẹ̀.”

Tàbí “ṣe dáadáa.”

Ní Gíríìkì Diʹke, ó ṣeé ṣe kó máa tọ́ka sí abo ọlọ́run ẹ̀san tàbí kó tọ́ka sí ìdájọ́ òdodo láwọn ọ̀nà míì téèyàn lè ronú kàn.

Wo Àfikún A3.

Tàbí “pẹ̀lú ìgboyà.”

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́