ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • nwt Jóòbù 1:1-42:17
  • Jóòbù

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Jóòbù
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
Jóòbù

JÓÒBÙ

1 Ọkùnrin kan wà ní ilẹ̀ Úsì tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Jóòbù.*+ Olódodo àti olóòótọ́* èèyàn+ ni; ó bẹ̀rù Ọlọ́run, ó sì kórìíra ohun tó burú.+ 2 Ó bí ọmọkùnrin méje àti ọmọbìnrin mẹ́ta. 3 Ẹran ọ̀sìn rẹ̀ jẹ́ ẹgbẹ̀rún méje (7,000) àgùntàn, ẹgbẹ̀rún mẹ́ta (3,000) ràkúnmí, ẹgbẹ̀rún kan (1,000) màlúù* àti ọgọ́rùn-ún márùn-ún (500) kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́,* ó tún ní àwọn ìránṣẹ́ tó pọ̀ gan-an débi pé òun ló wá lọ́lá jù lọ nínú gbogbo àwọn ará Ìlà Oòrùn.

4 Ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ máa ń se àsè ní ilé wọn lọ́jọ́ tó bá yàn.* Wọ́n máa ń pe àwọn arábìnrin wọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta pé kí wọ́n wá bá wọn jẹ, kí wọ́n sì jọ mu. 5 Tí àwọn ọjọ́ tí wọ́n ń jẹ àsè bá ti parí, Jóòbù máa ń ránṣẹ́ sí wọn kó lè sọ wọ́n di mímọ́. Ó máa dìde ní àárọ̀ kùtù, á sì rú ẹbọ sísun+ torí ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn. Torí Jóòbù máa ń sọ pé, “Bóyá àwọn ọmọ mi ti dẹ́ṣẹ̀, tí wọ́n sì ti bú Ọlọ́run nínú ọkàn wọn.” Ohun tí Jóòbù máa ń ṣe ní gbogbo ìgbà nìyẹn.+

6 Ó wá di ọjọ́ tí àwọn ọmọ Ọlọ́run tòótọ́*+ ń wọlé láti dúró níwájú Jèhófà,+ Sátánì+ náà sì wọlé sáàárín wọn.+

7 Jèhófà bi Sátánì pé: “Ibo lo ti ń bọ̀?” Sátánì dá Jèhófà lóhùn pé: “Látinú ayé, mo lọ káàkiri, mo sì rìn káàkiri nínú rẹ̀.”+ 8 Jèhófà sì bi Sátánì pé: “Ṣé o ti kíyè sí* Jóòbù ìránṣẹ́ mi? Kò sí ẹni tó dà bíi rẹ̀ ní ayé. Olódodo àti olóòótọ́* èèyàn+ ni, ó bẹ̀rù Ọlọ́run, ó sì kórìíra ohun tó burú.” 9 Ni Sátánì bá dá Jèhófà lóhùn pé: “Ṣé lásán ni Jóòbù ń bẹ̀rù Ọlọ́run ni?+ 10 Ṣebí o ti ṣe ọgbà yí i ká láti dáàbò bo òun,+ ilé rẹ̀ àti gbogbo ohun tó ní? O ti bù kún iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀,+ ẹran ọ̀sìn rẹ̀ sì ti pọ̀ gan-an ní ilẹ̀ náà. 11 Àmọ́, kí nǹkan lè yí pa dà, na ọwọ́ rẹ, kí o sì kọ lu gbogbo ohun tó ní, ó dájú pé ó máa bú ọ níṣojú rẹ gan-an.” 12 Jèhófà wá sọ fún Sátánì pé: “Wò ó! Gbogbo ohun tó ní wà ní ọwọ́ rẹ.* Àmọ́, o ò gbọ́dọ̀ fọwọ́ kan ọkùnrin náà fúnra rẹ̀!” Ni Sátánì bá jáde kúrò níwájú* Jèhófà.+

13 Ní ọjọ́ tí àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin Jóòbù ń jẹun, tí wọ́n sì ń mu wáìnì ní ilé ẹ̀gbọ́n wọn àgbà tó jẹ́ ọkùnrin,+ 14 ìránṣẹ́ kan wá bá Jóòbù, ó sì sọ pé: “Àwọn màlúù ń túlẹ̀, àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ sì ń jẹko lẹ́gbẹ̀ẹ́ wọn, 15 ni àwọn Sábéà bá gbógun dé, wọ́n kó wọn, wọ́n sì fi idà pa àwọn ìránṣẹ́. Èmi nìkan ló yè bọ́, tí mo sì wá sọ fún ọ.”

16 Bó ṣe ń sọ̀rọ̀ lọ́wọ́, ẹlòmíì dé, ó sì sọ pé: “Iná ti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá* láti ọ̀run, ó bọ́ sáàárín àwọn àgùntàn àti àwọn ìránṣẹ́, ó sì jó wọn run! Èmi nìkan ló yè bọ́, tí mo sì wá sọ fún ọ.”

17 Bó ṣe ń sọ̀rọ̀ lọ́wọ́, ẹlòmíì dé, ó sì sọ pé: “Àwọn ará Kálídíà+ pín ara wọn sí àwùjọ mẹ́ta, wọ́n ya bo àwọn ràkúnmí, wọ́n sì kó wọn, wọ́n wá fi idà pa àwọn ìránṣẹ́. Èmi nìkan ni mo yè bọ́, tí mo sì wá sọ fún ọ.”

18 Bó ṣe ń sọ̀rọ̀ lọ́wọ́, ẹlòmíì tún dé, ó sì sọ pé: “Àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin rẹ ń jẹun, wọ́n sì ń mu wáìnì ní ilé ẹ̀gbọ́n wọn àgbà tó jẹ́ ọkùnrin. 19 Ni ìjì tó lágbára bá fẹ́ wá lójijì láti aginjù, ó fẹ́ lu igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ilé náà, ilé náà sì wó lu àwọn ọmọ náà, wọ́n sì kú. Èmi nìkan ló yè bọ́, tí mo sì wá sọ fún ọ.”

20 Ni Jóòbù bá dìde, ó fa aṣọ rẹ̀ ya, ó gé irun orí rẹ̀; ó wólẹ̀, ó sì forí balẹ̀, 21 ó wá sọ pé:

“Ìhòòhò ni mo jáde látinú ikùn ìyá mi,

Ìhòòhò ni màá sì pa dà.+

Jèhófà ti fúnni,+ Jèhófà sì ti gbà á.

Ká máa yin orúkọ Jèhófà títí lọ.”

22 Nínú gbogbo ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí, Jóòbù ò dẹ́ṣẹ̀, kò sì fẹ̀sùn kan Ọlọ́run pé ó ṣe ohun tí kò dáa.*

2 Lẹ́yìn náà, nígbà tó di ọjọ́ tí àwọn ọmọ Ọlọ́run tòótọ́*+ ń wọlé láti dúró níwájú Jèhófà,+ Sátánì náà wọlé sáàárín wọn kó lè dúró níwájú Jèhófà.+

2 Jèhófà bi Sátánì pé: “Ibo lo ti ń bọ̀?” Sátánì dá Jèhófà lóhùn pé: “Látinú ayé, mo lọ káàkiri, mo sì rìn káàkiri nínú rẹ̀.”+ 3 Jèhófà sì bi Sátánì pé: “Ṣé o ti kíyè sí* Jóòbù ìránṣẹ́ mi? Kò sí ẹni tó dà bíi rẹ̀ ní ayé. Olódodo àti olóòótọ́* èèyàn+ ni, ó bẹ̀rù Ọlọ́run, ó sì kórìíra ohun tó burú. Kò fi ìwà títọ́ rẹ̀ sílẹ̀ rárá,+ bó tiẹ̀ jẹ́ pé o fẹ́ sún mi+ láti pa á run* láìnídìí.” 4 Àmọ́, Sátánì dá Jèhófà lóhùn pé: “Awọ dípò awọ. Gbogbo ohun tí èèyàn bá ní ló máa fi dípò ẹ̀mí* rẹ̀. 5 Àmọ́, kí nǹkan lè yí pa dà, na ọwọ́ rẹ, kí o sì kọ lu egungun àti ara rẹ̀, ó dájú pé ó máa bú ọ níṣojú rẹ gan-an.”+

6 Jèhófà wá sọ fún Sátánì pé: “Wò ó! Ó wà ní ọwọ́ rẹ!* Àmọ́, o ò gbọ́dọ̀ gba ẹ̀mí* rẹ̀!” 7 Ni Sátánì bá jáde kúrò níwájú* Jèhófà, ó sì fi eéwo tó ń roni lára*+ kọ lu Jóòbù láti àtẹ́lẹsẹ̀ rẹ̀ títí dé àtàrí rẹ̀. 8 Jóòbù wá mú àfọ́kù ìkòkò, ó sì fi ń họ ara rẹ̀, ó wá jókòó sínú eérú.+

9 Níkẹyìn, ìyàwó rẹ̀ sọ fún un pé: “Ṣé pé o ò tíì fi ìwà títọ́ rẹ sílẹ̀? Sọ̀rọ̀ òdì sí Ọlọ́run, kí o sì kú!” 10 Àmọ́ Jóòbù sọ fún un pé: “Ò ń sọ̀rọ̀ bí ọ̀kan lára àwọn obìnrin tí kò nírònú. Tí a bá gba ohun rere lọ́wọ́ Ọlọ́run tòótọ́, ṣé kò yẹ ká tún gba ohun búburú?”+ Nínú gbogbo ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí, Jóòbù kò fi ẹnu rẹ̀ dẹ́ṣẹ̀.+

11 Àwọn ọ̀rẹ́* Jóòbù mẹ́ta gbọ́ nípa gbogbo àjálù tó dé bá a, kálukú sì wá láti ibi tó ń gbé, Élífásì+ ará Témánì, Bílídádì+ ọmọ Ṣúáhì+ àti Sófárì+ ọmọ Náámà. Wọ́n ṣàdéhùn láti pàdé, kí wọ́n lè lọ bá Jóòbù kẹ́dùn, kí wọ́n sì tù ú nínú. 12 Nígbà tí wọ́n rí i lọ́ọ̀ọ́kán, wọn ò dá a mọ̀. Ni wọ́n bá bú sẹ́kún, wọ́n fa aṣọ wọn ya, wọ́n sì da iyẹ̀pẹ̀ sínú afẹ́fẹ́ àti sórí ara wọn.+ 13 Wọ́n sì jókòó sílẹ̀ lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀ fún ọ̀sán méje àti òru méje. Ẹnì kankan ò bá a sọ̀rọ̀, torí wọ́n rí i pé ìrora rẹ̀ pọ̀ gan-an.+

3 Lẹ́yìn nǹkan wọ̀nyí, Jóòbù bẹ̀rẹ̀ sí í sọ̀rọ̀, ó sì ń fi ọjọ́ tí wọ́n bí i gégùn-ún.*+ 2 Jóòbù sọ pé:

 3 “Kí ọjọ́ tí wọ́n bí mi + ṣègbé,

Àti òru tí ẹnì kan sọ pé: ‘Wọ́n ti lóyún ọkùnrin kan!’

 4 Kí ọjọ́ yẹn ṣókùnkùn.

Kí Ọlọ́run lókè má ka ọjọ́ yẹn sí;

Kí ìmọ́lẹ̀ má tàn sórí rẹ̀ rárá.

 5 Kí òkùnkùn biribiri* gbà á pa dà.

Kí òjò ṣú bò ó.

Kí ohunkóhun tó ń mú ojúmọ́ ṣókùnkùn dẹ́rù bà á.

 6 Kí ìṣúdùdù gba òru yẹn;+

Kó má ṣe yọ̀ láàárín àwọn ọjọ́ tó wà nínú ọdún,

Kí wọ́n má sì kà á mọ́ àwọn oṣù.

 7 Àní, kí òru yẹn yàgàn!

Ká má ṣe gbọ́ igbe ayọ̀ kankan ní òru yẹn.

 8 Kí àwọn tó ń fi ọjọ́ gégùn-ún fi í gégùn-ún,

Àwọn tó lè mú kí Léfíátánì*+ sọ jí.

 9 Kí àwọn ìràwọ̀ rẹ̀ ṣókùnkùn ní ìdájí;

Kó dúró de ìmọ́lẹ̀, àmọ́ kí ìrètí rẹ̀ já sí asán,

Kó má sì rí ìtànṣán ìmọ́lẹ̀ òwúrọ̀.

10 Torí kò ti àwọn ilẹ̀kùn ilé ọlẹ̀ ìyá mi;+

Kò sì pa ojú mi mọ́ kúrò nínú wàhálà.

11 Kí ló dé tí mi ò kú nígbà tí wọ́n bí mi?

Kí ló dé tí mi ò ṣègbé nígbà tí mo jáde látinú ikùn?+

12 Kí ló dé tí orúnkún tó gbà mí fi wà,

Tí ọmú tí màá mu sì wà?

13 Torí mi ò bá máa dùbúlẹ̀ báyìí láìsí ìyọlẹ́nu;+

Mi ò bá máa sùn, kí n sì máa sinmi+

14 Pẹ̀lú àwọn ọba ayé àti àwọn agbani-nímọ̀ràn wọn,

Tí wọ́n kọ́ àwọn ibi tó ti di àwókù báyìí fún ara wọn,*

15 Tàbí pẹ̀lú àwọn ìjòyè tó ní wúrà,

Àwọn tí fàdákà kún ilé wọn.

16 Àbí kí ló dé tí oyún mi ò ti bà jẹ́ kí wọ́n tó mọ̀,

Bí àwọn ọmọ tí kò rí ìmọ́lẹ̀ rárá?

17 Ibẹ̀ ni àwọn ẹni burúkú pàápàá ti bọ́ lọ́wọ́ ìdààmú;

Ibẹ̀ ni àwọn tí kò lókun ti ń sinmi.+

18 Ibẹ̀ ni ara ti tu àwọn ẹlẹ́wọ̀n pa pọ̀;

Wọn ò gbọ́ ohùn ẹni tó ń fipá kó wọn ṣiṣẹ́.

19 Ẹni kékeré àti ẹni ńlá ò jura wọn lọ níbẹ̀,+

Ẹrú sì dòmìnira lọ́wọ́ ọ̀gá rẹ̀.

20 Kí ló dé tó fún ẹni tí ìyà ń jẹ ní ìmọ́lẹ̀,

Tó sì fún àwọn tó ní ẹ̀dùn ọkàn*+ ní ìyè?

21 Kí ló dé tí wọ́n ń retí ikú, àmọ́ tí kò dé?+

Wọ́n ń wá a ju bí wọ́n ṣe ń wá ìṣúra tó fara pa mọ́ sínú ilẹ̀,

22 Àwọn tí inú wọn ń dùn gidigidi,

Tí wọ́n ń yọ̀ nígbà tí wọ́n rí sàréè.

23 Kí ló dé tó fún ẹni tó ṣìnà ní ìmọ́lẹ̀,

Ẹni tí Ọlọ́run ti sé mọ́?+

24 Ẹ̀dùn ọkàn ti dípò oúnjẹ mi,+

Ìkérora mi+ sì ń tú jáde bí omi.

25 Torí ohun tí mo bẹ̀rù ti dé bá mi,

Ohun tó sì ń já mi láyà ti ṣẹlẹ̀ sí mi.

26 Mi ò ní àlàáfíà, ọkàn mi ò balẹ̀, mi ò sì sinmi,

Síbẹ̀, wàhálà ò yéé dé bá mi.”

4 Élífásì+ ará Témánì wá fèsì pé:

 2 “Tí ẹnì kan bá fẹ́ bá ọ sọ̀rọ̀, ṣebí wàá ní sùúrù?

Àbí ta ló lè dákẹ́ kó má sọ̀rọ̀?

 3 Òótọ́ ni pé o ti tọ́ ọ̀pọ̀ èèyàn sọ́nà,

O sì máa ń fún àwọn ọwọ́ tí kò lágbára lókun.

 4 Ọ̀rọ̀ rẹ máa ń gbé ẹnikẹ́ni tó bá kọsẹ̀ dìde,

O sì máa ń fún àwọn tí orúnkún wọn yẹ̀ lókun.

 5 Àmọ́ ó ti ṣẹlẹ̀ sí ọ báyìí, ó sì wá mu ọ́ lómi;*

Ó kàn ọ́, ìdààmú sì bá ọ.

 6 Ṣé ìbẹ̀rù tí o ní fún Ọlọ́run kò fi ọ́ lọ́kàn balẹ̀ ni?

Ṣé ìwà títọ́+ rẹ ò fún ọ ní ìrètí ni?

 7 Jọ̀ọ́ rántí: Aláìṣẹ̀ wo ló ṣègbé rí?

Ìgbà wo ni àwọn adúróṣinṣin pa run rí?

 8 Ohun tí mo rí ni pé àwọn tó ń túlẹ̀ láti gbin* ohun tó burú

Àti àwọn tó ń gbin wàhálà máa kórè ohun tí wọ́n bá gbìn.

 9 Èémí Ọlọ́run mú kí wọ́n ṣègbé,

Ìbínú rẹ̀ tó le sì mú kí wọ́n wá sí òpin.

10 Kìnnìún ń ké ramúramù, ọmọ kìnnìún sì ń kùn,

Àmọ́ eyín àwọn kìnnìún tó lágbára* pàápàá kán.

11 Kìnnìún ṣègbé torí kò rí ẹran pa jẹ,

Àwọn ọmọ kìnnìún sì tú ká.

12 A sọ ọ̀rọ̀ kan fún mi ní àṣírí,

A sì sọ ọ́ sí mi létí wúyẹ́wúyẹ́.

13 Nínú ìran tí mo rí ní òru, tó ń da ọkàn láàmú,

Nígbà tí àwọn èèyàn ti sùn lọ fọnfọn,

14 Mo bẹ̀rẹ̀ sí í gbọ̀n rìrì lákọlákọ,

Ìbẹ̀rù bò mí wọnú egungun.

15 Ẹ̀mí kan kọjá lójú mi;

Irun ara mi dìde.

16 Ó wá dúró sójú kan,

Àmọ́ mi ò dá a mọ̀.

Ohun kan wà níwájú mi;

Gbogbo nǹkan pa rọ́rọ́, mo wá gbọ́ ohùn kan tó sọ pé:

17 ‘Ṣé ẹni kíkú lè jẹ́ olódodo ju Ọlọ́run lọ?

Ṣé ẹnì kan lè mọ́ ju Ẹni tó dá a lọ?’

18 Wò ó! Kò ní ìgbàgbọ́ nínú àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀,

Ó sì ń wá àṣìṣe àwọn áńgẹ́lì* rẹ̀.

19 Mélòómélòó wá ni àwọn tó ń gbé ilé alámọ̀,

Tí ìpìlẹ̀ wọn wà nínú iyẹ̀pẹ̀,+

Tí wọ́n rọrùn láti tẹ̀ rẹ́ bí òólá!*

20 A tẹ̀ wọ́n rẹ́ pátápátá láti òwúrọ̀ ṣúlẹ̀;

Wọ́n ṣègbé títí láé, ẹnì kankan ò sì kíyè sí i.

21 Ṣebí wọ́n dà bí àgọ́ tí wọ́n fa okùn rẹ̀ yọ?

Wọ́n kú láìní ọgbọ́n.

5 “Jọ̀ọ́ pè! Ṣé ẹnikẹ́ni dá ọ lóhùn?

Èwo nínú àwọn ẹni mímọ́ lo máa yíjú sí?

 2 Ìbínú tí òmùgọ̀ dì sínú ló máa pa á,

Ìlara ló sì máa pa ẹni tí kò láròjinlẹ̀.

 3 Mo ti rí i tí òmùgọ̀ ta gbòǹgbò,

Àmọ́ lójijì, wọ́n gégùn-ún fún ibi tó ń gbé.

 4 Àwọn ọmọ rẹ̀ jìnnà sí ààbò,

Wọ́n sì tẹ̀ wọ́n rẹ́ ní ẹnubodè+ ìlú láìsí ẹni tó máa gbà wọ́n sílẹ̀.

 5 Ẹni tí ebi ń pa jẹ ohun tó kórè,

Àárín àwọn ẹ̀gún pàápàá ló ti mú un,

Wọ́n dẹkùn mú àwọn ohun ìní wọn.

 6 Torí ohun tó léwu kì í hù látinú iyẹ̀pẹ̀,

Wàhálà kì í sì í hù látinú ilẹ̀.

 7 Torí inú wàhálà ni wọ́n ń bí èèyàn sí,

Bó ṣe dájú pé iná máa ń ta pàrà sókè.

 8 Àmọ́ màá mú ọ̀rọ̀ mi tọ Ọlọ́run lọ,

Ọlọ́run sì ni màá gbé ẹjọ́ mi lọ bá,

 9 Sọ́dọ̀ Ẹni tó ń ṣe àwọn ohun ńlá àtàwọn ohun àwámáridìí,

Àwọn ohun àgbàyanu tí kò níye.

10 Ó ń rọ òjò sí ayé,

Ó sì ń bomi rin oko.

11 Ó ń gbé ẹni tó rẹlẹ̀ ga,

Ó sì ń gbé ẹni tí inú rẹ̀ bà jẹ́ sókè fún ìgbàlà.

12 Ó ń sọ ohun tí àwọn ọlọ́gbọ́n ẹ̀wẹ́ ń hùmọ̀ di asán,

Kí iṣẹ́ ọwọ́ wọn má bàa yọrí sí rere.

13 Ó ń mú àwọn ọlọ́gbọ́n nínú ọgbọ́n ẹ̀wẹ́ wọn,+

Kó lè da ète àwọn ọlọ́gbọ́n rú.

14 Wọ́n rí òkùnkùn ní ọ̀sán,

Wọ́n sì ń táràrà kiri ní ọ̀sán gangan bíi pé òru ni.

15 Ó ń gbani lọ́wọ́ idà ẹnu wọn,

Ó ń gba aláìní lọ́wọ́ alágbára,

16 Kí ẹni tó rẹlẹ̀ lè ní ìrètí,

Àmọ́ a pa àìṣòdodo lẹ́nu mọ́.

17 Wò ó! Aláyọ̀ ni ẹni tí Ọlọ́run bá wí;

Torí náà, má ṣe kọ ìbáwí Olódùmarè!

18 Torí ó ń fa ìrora, àmọ́ ó ń di ọgbẹ́;

Ó ń fọ́ nǹkan sí wẹ́wẹ́, àmọ́ ó ń fi ọwọ́ ara rẹ̀ ṣe ìwòsàn.

19 Ó máa gbà ọ́ lọ́wọ́ àjálù mẹ́fà,

Ìkeje pàápàá kò ní ṣe ọ́ lọ́ṣẹ́.

20 Ó máa rà ọ́ pa dà lọ́wọ́ ikú lásìkò ìyàn

Àti lọ́wọ́ agbára idà nígbà ogun.

21 Ó máa dáàbò bò ọ́ lọ́wọ́ pàṣán ahọ́n,+

O ò sì ní bẹ̀rù ìparun nígbà tó bá dé.

22 O máa fi ìparun àti ebi rẹ́rìn-ín,

O ò sì ní bẹ̀rù àwọn ẹran inú igbó.

23 Torí àwọn òkúta inú pápá kò ní ṣe ọ́ léṣe,*

Àwọn ẹranko sì máa wà ní àlàáfíà pẹ̀lú rẹ.

24 O máa mọ̀ pé kò sí ewu ní àgọ́ rẹ,*

O ò sì ní wá ohunkóhun ní àwátì tí o bá ń yẹ ibi ìjẹko rẹ wò.

25 O máa bí ọmọ tó pọ̀,

Àwọn àtọmọdọ́mọ rẹ á sì pọ̀ bí ewéko ilẹ̀.

26 Ara rẹ ṣì máa le koko nígbà tí o bá lọ sínú sàréè,

Bí ìtí ọkà tí wọ́n kó jọ ní àkókò wọn.

27 Wò ó! A ti wádìí èyí, bẹ́ẹ̀ ló sì rí.

Fetí sílẹ̀, kí o sì fara mọ́ ọn.”

6 Jóòbù wá fèsì pé:

 2 “Ká ní wọ́n lè díwọ̀n ìrora mi+ látòkè délẹ̀ ni,

Kí wọ́n sì gbé òun àti àjálù mi sórí òṣùwọ̀n!

 3 Ó ti wá wúwo ju iyanrìn òkun lọ báyìí.

Ìdí nìyẹn tí ọ̀rọ̀ mi fi jẹ́ ọ̀rọ̀ ẹhànnà.*+

 4 Torí àwọn ọfà Olódùmarè ti gún mi,

Ẹ̀mí mi sì ń mu oró wọn;+

Ohun tó ń fa ìpayà látọ̀dọ̀ Ọlọ́run ti kóra jọ lòdì sí mi.

 5 Ṣé kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ igbó+ máa ké tó bá rí koríko jẹ,

Àbí ṣé akọ màlúù máa dún tó bá rí oúnjẹ ẹran jẹ?

 6 Ṣé èèyàn lè jẹ oúnjẹ tí kò dùn láìfi iyọ̀ sí i,

Àbí ṣé adùn wà nínú omi ewéko málò?

 7 Mi* ò fọwọ́ kan irú àwọn nǹkan yẹn.

Wọ́n dà bí ohun tó ba oúnjẹ mi jẹ́.

 8 Ká ní ọwọ́ mi lè tẹ ohun tí mo béèrè ni,

Kí Ọlọ́run sì ṣe ohun tí mo fẹ́ fún mi!

 9 Pé kí Ọlọ́run ṣe tán láti tẹ̀ mí rẹ́,

Kó na ọwọ́ rẹ̀, kó sì pa mí dà nù!+

10 Torí ìyẹn gan-an máa tù mí nínú;

Màá fò sókè tayọ̀tayọ̀ láìka ìrora tí kò lọ sí,

Torí mi ò sọ pé irọ́ ni àwọn ọ̀rọ̀ Ẹni Mímọ́.+

11 Ṣé agbára mi gbé e láti máa dúró?+

Òpin wo ló máa dé bá mi, tí màá ṣì fi wà láàyè?*

12 Ṣé mo lágbára bí òkúta?

Àbí bàbà ni ẹran ara mi?

13 Ṣé mo lè ran ara mi lọ́wọ́ rárá,

Nígbà tí a ti lé gbogbo ohun tí mo fi ń ti ara mi lẹ́yìn jìnnà sí mi?

14 Ẹnikẹ́ni tí kò bá fi ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ hàn sí ẹnì kejì rẹ̀,+

Kò ní bẹ̀rù Olódùmarè.+

15 Àwọn arákùnrin mi ti di ọ̀dàlẹ̀+ bí odò ìgbà òtútù,

Bí àwọn omi odò ìgbà òtútù tó gbẹ.

16 Yìnyín mú kó ṣókùnkùn,

Yìnyín tó sì ń yọ́ fara pa mọ́ sínú wọn.

17 Àmọ́ ní àsìkò tó yẹ, wọn ò lómi mọ́, wọ́n sì wá sí òpin;

Nígbà ẹ̀ẹ̀rùn, wọ́n gbẹ dà nù.

18 Ipa odò wọn gba ibòmíì;

Wọ́n ṣàn lọ sínú aṣálẹ̀, wọ́n sì dópin.

19 Àwọn ará Témà+ tí wọ́n ń rìnrìn àjò ń wá wọn,

Àwọn arìnrìn-àjò láti Ṣébà*+ ń dúró dè wọ́n.

20 Ojú tì wọ́n torí pé ìgbẹ́kẹ̀lé wọn ti dòfo;

Wọ́n dé ibẹ̀, àmọ́ òfo ni wọ́n bá.

21 Bí ẹ̀yin náà ṣe wá rí lójú mi nìyẹn;+

Ẹ rí bí àjálù tó bá mi ṣe le tó,* ẹ̀rù sì bà yín.+

22 Ṣé mo sọ pé, ‘Ẹ fún mi ní nǹkan,’

Àbí mo tọrọ ẹ̀bùn látinú ọrọ̀ yín?

23 Ṣé mo ní kí ẹ gbà mí lọ́wọ́ ọ̀tá,

Àbí mo ní kí ẹ gbà mí* lọ́wọ́ àwọn tó ń fìyà jẹ mí?

24 Ẹ kọ́ mi, màá sì dákẹ́;+

Ẹ jẹ́ kí n mọ àṣìṣe mi.

25 Òótọ́ ọ̀rọ̀ kì í dunni!+

Àmọ́ kí ni ìbáwí yín wúlò fún?+

26 Ṣé ẹ̀ ń gbèrò láti bá mi wí torí ọ̀rọ̀ mi ni,

Ọ̀rọ̀ tí ẹni tí ìdààmú bá ń sọ,+ tí afẹ́fẹ́ sì ń fẹ́ dà nù?

27 Ẹ máa ṣẹ́ kèké lé ọmọ aláìlóbìí*+ pàápàá,

Ẹ sì máa ta ọ̀rẹ́ yín!*+

28 Torí náà, ẹ yíjú wò mí,

Mi ò ní parọ́ fún yín.

29 Ẹ jọ̀ọ́, ẹ tún inú rò, ẹ má ṣe dá mi lẹ́bi,

Àní, ẹ tún inú rò, torí òdodo mi ò tíì yí pa dà.

30 Ṣé ahọ́n mi ń sọ ohun tí kò tọ́ ni?

Ṣé agbára ìtọ́wò ẹnu mi ò mọ̀ pé nǹkan ti ṣẹlẹ̀ ni?

7 “Ǹjẹ́ ìgbésí ayé ẹni kíkú lórí ilẹ̀ kò dà bí iṣẹ́ àṣekára tó pọn dandan?

Ṣé kì í ṣe bíi ti alágbàṣe ni àwọn ọjọ́ rẹ̀ rí?+

 2 Ó ń retí òjìji bíi ti ẹrú,

Ó sì ń dúró de owó iṣẹ́ rẹ̀ bíi ti alágbàṣe.+

 3 Torí náà, a ti yan àwọn oṣù asán fún mi,

Àwọn òru ìbànújẹ́ ni a sì ti kà sílẹ̀ fún mi.+

 4 Nígbà tí mo dùbúlẹ̀, mo béèrè pé, ‘Ìgbà wo ni màá dìde?’+

Àmọ́ bí òru náà ṣe ń falẹ̀, ṣe ni mò ń yí kiri títí ilẹ̀ fi mọ́.*

 5 Ìdin àti iyẹ̀pẹ̀ tó ṣù pọ̀ bo ara mi;+

Gbogbo awọ ara mi ti sé èépá, ó sì ń ṣọyún.+

 6 Àwọn ọjọ́ mi ń yára sáré ju ohun èlò tí wọ́n fi ń hun aṣọ,+

Wọ́n sì dópin láìnírètí.+

 7 Rántí pé afẹ́fẹ́ ni ẹ̀mí mi,+

Pé ojú mi kò tún ní rí ayọ̀* mọ́.

 8 Ojú tó rí mi báyìí kò ní rí mi mọ́;

Ojú rẹ máa wá mi, àmọ́ mi ò ní sí mọ́.+

 9 Bí ìkùukùu tó ń pa rẹ́ lọ, tó sì wá pòórá,

Ẹni tó lọ sí Isà Òkú* kì í pa dà wá.+

10 Kò ní pa dà sí ilé rẹ̀ mọ́,

Ibùgbé rẹ̀ kò sì ní mọ̀ ọ́n mọ́.+

11 Torí náà, mi ò ní pa ẹnu mi mọ́.

Màá sọ̀rọ̀ látinú ìrora ẹ̀mí mi,

Màá ṣàròyé látinú ẹ̀dùn ọkàn* tó bá mi!+

12 Ṣé èmi ni òkun tàbí ẹran ńlá inú òkun,

Tí o fi máa yan ẹ̀ṣọ́ tì mí?

13 Nígbà tí mo sọ pé, ‘Àga mi máa tù mí nínú;

Ibùsùn mi máa bá mi dín ìbànújẹ́ mi kù,’

14 O wá fi àwọn àlá dẹ́rù bà mí,

O sì fi àwọn ìran dáyà já mi,

15 Tó fi jẹ́ pé mo* fara mọ́ ọn kí wọ́n sé mi léèémí,

Àní, ikú dípò ara mi yìí.*+

16 Mo kórìíra ayé mi gidigidi;+ mi ò fẹ́ wà láàyè mọ́.

Fi mí sílẹ̀, torí àwọn ọjọ́ mi dà bí èémí.+

17 Kí ni ẹni kíkú jẹ́ tí o fi máa rí tiẹ̀ rò,

Tí o sì máa fún un ní àfiyèsí?*+

18 Kí ló dé tí ò ń yẹ̀ ẹ́ wò ní àràárọ̀,

Tí o sì ń dán an wò ní ìṣẹ́jú-ìṣẹ́jú?+

19 Ṣé o ò ní gbójú kúrò lọ́dọ̀ mi ni,

Kí o sì fi mí sílẹ̀ kí n lè ráyè gbé itọ́ mì?+

20 Tí mo bá ṣẹ̀, ṣé mo lè ṣe ọ́ níbi, ìwọ Ẹni tó ń kíyè sí aráyé?+

Kí ló dé tí o dájú sọ mí?

Àbí mo ti di ìnira fún ọ ni?

21 Kí ló dé tí o ò dárí ẹ̀ṣẹ̀ mi jì,

Kí o sì gbójú fo àṣìṣe mi?

Torí láìpẹ́, màá dùbúlẹ̀ sínú erùpẹ̀,+

O máa wá mi, àmọ́ mi ò ní sí mọ́.”

8 Bílídádì+ ọmọ Ṣúáhì+ wá fèsì pé:

 2 “Ìgbà wo lo ò ní sọ̀rọ̀ báyìí mọ́?+

Ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ dà bí ìjì tó le!

 3 Ṣé Ọlọ́run máa yí ìdájọ́ po ni,

Àbí Olódùmarè máa yí òdodo po?

 4 Tó bá jẹ́ pé àwọn ọmọ rẹ ti ṣẹ̀ ẹ́,

Ó jẹ́ kí wọ́n jìyà ìwà ọ̀tẹ̀ wọn;*

 5 Àmọ́ tí o bá lè yíjú sí Ọlọ́run,+

Kí o sì bẹ Olódùmarè pé kó ṣojúure sí ọ,

 6 Tó bá jẹ́ pé òótọ́ lo mọ́, tí o sì jẹ́ olódodo,+

Ó máa fetí sí ọ,*

Ó sì máa dá ọ pa dà sí ibi tó tọ́ sí ọ.

 7 Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ìbẹ̀rẹ̀ rẹ kéré,

Ọjọ́ iwájú rẹ máa dára gan-an.+

 8 Jọ̀ọ́, béèrè lọ́wọ́ ìran àtijọ́,

Kí o sì fiyè sí àwọn ohun tí àwọn bàbá wọn rí.+

 9 Torí ọmọ àná lásán ni wá, a ò sì mọ nǹkan kan,

Torí pé òjìji ni àwọn ọjọ́ ayé wa.

10 Ṣé wọn ò ní kọ́ ọ ni,

Kí wọ́n sì sọ ohun tí wọ́n mọ̀ fún ọ?*

11 Ṣé òrépèté lè dàgbà níbi tí kò sí irà?

Ṣé esùsú* lè dàgbà láìsí omi?

12 Nígbà tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń rú yọ, tí wọn ò tíì já a,

Ó máa gbẹ dà nù ṣáájú gbogbo ewéko yòókù.

13 Ohun tó máa ṣẹlẹ̀ sí gbogbo àwọn tó gbàgbé Ọlọ́run nìyẹn,*

Torí ìrètí ẹni tí kò mọ Ọlọ́run* máa ṣègbé,

14 Ẹni tí ìgbẹ́kẹ̀lé rẹ̀ já sí asán,

Tí ìgbẹ́kẹ̀lé rẹ̀ ò sì lágbára, àfi bí òwú* aláǹtakùn.

15 Ó máa fara ti ilé rẹ̀, àmọ́ kò ní lè dúró;

Ó máa fẹ́ dì í mú, àmọ́ kò ní wà pẹ́.

16 Ó dà bí ewéko tútù nínú oòrùn,

Àwọn ẹ̀ka rẹ̀ sì gbalẹ̀ nínú ọgbà.+

17 Gbòǹgbò rẹ̀ lọ́ mọ́ra láàárín òkúta tí wọ́n kó jọ pelemọ;

Ó ń wá ilé láàárín àwọn òkúta.*

18 Àmọ́ tí wọ́n bá ti fà á tu* kúrò níbi tó wà,

Ibẹ̀ máa kọ̀ ọ́ sílẹ̀, ó sì máa sọ fún un pé, ‘Mi ò rí ọ rí.’+

19 Àní, bí a ò ṣe ní rí i mọ́+ nìyẹn;*

Àwọn míì á wá hù jáde látinú ilẹ̀.

20 Ó dájú pé Ọlọ́run ò ní kọ àwọn olóòótọ́* sílẹ̀;

Kò sì ní ti àwọn ẹni ibi lẹ́yìn,*

21 Torí ó ṣì máa fi ẹ̀rín kún ẹnu rẹ,

Ó sì máa mú kí ètè rẹ kígbe ayọ̀.

22 Ìtìjú máa bo àwọn tó kórìíra rẹ,

Àgọ́ àwọn ẹni burúkú ò sì ní sí mọ́.”

9 Jóòbù fèsì pé:

 2 “Lóòótọ́, mo mọ̀ pé bẹ́ẹ̀ ló rí.

Àmọ́ báwo ni ẹni kíkú ṣe lè jàre tó bá bá Ọlọ́run ṣe ẹjọ́?+

 3 Tí ẹnì kan bá tiẹ̀ fẹ́ bá A jiyàn,*+

Onítọ̀hún ò ní lè dáhùn ọ̀kan nínú ẹgbẹ̀rún (1,000) ìbéèrè tí Ó bá bi í.

 4 Ọlọ́gbọ́n ni,* ó sì ní agbára gan-an.+

Ta ló lè ta kò ó, tí kò ní fara pa?+

 5 Ó ń ṣí àwọn òkè nídìí* láìsí ẹni tó mọ̀;

Ó ń fi ìbínú dojú wọn dé.

 6 Ó ń mi ayé tìtì kúrò ní àyè rẹ̀,

Débi pé àwọn òpó rẹ̀ ń gbọ̀n rìrì.+

 7 Ó ń pàṣẹ pé kí oòrùn má ràn,

Ó sì ń dí ìmọ́lẹ̀ àwọn ìràwọ̀+ pa;

 8 Òun nìkan na ọ̀run jáde,+

Ó sì ń rìn lórí ìgbì tó ga lórí òkun.+

 9 Ó ṣe àgbájọ ìràwọ̀ Ááṣì,* Késílì* àti Kímà,*+

Pẹ̀lú àgbájọ ìràwọ̀ apá gúúsù ojú ọ̀run;*

10 Ó ń ṣe àwọn ohun ńlá àti àwọn ohun àwámáridìí,+

Àwọn ohun àgbàyanu tí kò ṣeé kà.+

11 Ó kọjá lẹ́gbẹ̀ẹ́ mi, mi ò sì rí i;

Ó kọjá síwájú mi, àmọ́ mi ò dá a mọ̀.

12 Tó bá já nǹkan gbà, ta ló lè dá a dúró?

Ta ló lè bi í pé, ‘Kí lò ń ṣe?’+

13 Ọlọ́run ò ní dáwọ́ ìbínú rẹ̀ dúró;+

Àwọn tó ń ran Ráhábù*+ lọ́wọ́ pàápàá máa tẹrí ba fún un.

14 Ǹjẹ́ kò wá yẹ kí n ṣọ́ àwọn ọ̀rọ̀ ẹnu mi

Tí mo bá ń dá a lóhùn láti bá a jiyàn!

15 Tí mo bá tiẹ̀ jàre, mi ò ní dá a lóhùn.+

Mi ò lè ṣe ju pé kí n bẹ adájọ́ mi* pé kó ṣàánú mi.

16 Tí mo bá ké pè é, ṣé ó máa dá mi lóhùn?

Mi ò rò pé ó máa fetí sí ohùn mi,

17 Torí ó fi ìjì wó mi mọ́lẹ̀,

Ó sì mú kí ọgbẹ́ mi pọ̀ sí i láìnídìí.+

18 Kò jẹ́ kí n mí;

Ó ń fi àwọn ohun tó korò kún inú mi.

19 Tó bá jẹ́ ti agbára, òun ni alágbára.+

Tó bá jẹ́ ti ìdájọ́ òdodo, ó sọ pé: ‘Ta ló lè yẹ̀ mí lọ́wọ́ wò?’*

20 Tí mo bá jàre, ẹnu mi máa dá mi lẹ́bi;

Tí mi ò bá tiẹ̀ fi ìwà títọ́ mi sílẹ̀,* ó máa dá mi lẹ́bi.*

21 Tí mi ò bá tiẹ̀ fi ìwà títọ́ mi sílẹ̀,* mi ò dá ara mi lójú;*

Ayé mi ti sú mi.*

22 Bákan náà ni gbogbo rẹ̀ rí. Ìdí nìyẹn tí mo fi sọ pé,

‘Bó ṣe ń pa aláìṣẹ̀* run ló ń pa ẹni burúkú run.’

23 Bí omi tó ya lójijì bá fa ikú òjijì,

Ó máa fi aláìmọwọ́-mẹsẹ̀ ṣe yẹ̀yẹ́ nígbà tó ń dààmú.

24 A ti fi ayé lé ẹni burúkú lọ́wọ́;+

Ó ń bo ojú àwọn adájọ́ rẹ̀.

Tí kì í bá ṣe òun, ta wá ni?

25 Àwọn ọjọ́ mi wá ń yára ju ẹni tó ń sáré;+

Wọ́n sá lọ láìrí ohun tó dáa.

26 Wọ́n ń yára bí ọkọ̀ ojú omi tí wọ́n fi esùsú* ṣe,

Bí ẹyẹ idì tó já ṣòòrò wálẹ̀ láti gbé ohun tó fẹ́ pa.

27 Tí mo bá sọ pé, ‘Màá gbàgbé àròyé tí mo ṣe,

Màá tújú ká, màá sì múnú ara mi dùn,’

28 Ẹ̀rù á ṣì máa bà mí torí gbogbo ìrora mi;+

Mo sì mọ̀ pé o ò ní kà mí sí aláìmọwọ́-mẹsẹ̀.

29 O máa sọ pé mo jẹ̀bi.*

Kí wá ni mo fẹ́ máa ṣe làálàá lásán fún?+

30 Tí mo bá fi omi yìnyín tó ń yọ́ wẹ ara mi,

Tí mo sì fi ọṣẹ* fọ ọwọ́ mi,+

31 O máa rì mí bọ kòtò,

Tí aṣọ mi pàápàá fi máa kórìíra mi.

32 Torí kì í ṣe èèyàn bíi tèmi tí màá fi dá a lóhùn,

Tí a fi jọ máa lọ sílé ẹjọ́.+

33 Kò sẹ́ni tó máa ṣèdájọ́* láàárín wa,

Tó máa jẹ́ adájọ́ wa.*

34 Ká ní kò ní lù mí mọ́ ni,*

Tí kò sì dáyà já mi,+

35 Màá sọ̀rọ̀ láìbẹ̀rù,

Torí ẹ̀rù kì í bà mí láti sọ̀rọ̀.

10 “Mo* kórìíra ayé mi gidigidi.+

Mi ò ní pa bó ṣe ń ṣe mi mọ́ra.

Màá sọ̀rọ̀ látinú ẹ̀dùn ọkàn* tó bá mi!

 2 Màá sọ fún Ọlọ́run pé: ‘Má ṣe dá mi lẹ́bi.

Jẹ́ kí n mọ ìdí tí o fi ń bá mi jà.

 3 Ṣé ó máa ṣe ọ́ láǹfààní tí o bá fìyà jẹni,

Tí o bá kórìíra iṣẹ́ ọwọ́ rẹ,+

Tí o sì fara mọ́ ìmọ̀ràn àwọn ẹni burúkú?

 4 Ṣé ojú rẹ dà bíi ti èèyàn ni,

Àbí o máa ń wo nǹkan bíi ti ẹni kíkú?

 5 Ṣé bí ọjọ́ àwọn ẹni kíkú ni àwọn ọjọ́ rẹ rí,

Àbí àwọn ọdún rẹ dà bíi ti èèyàn,+

 6 Tí o fi ń wá àṣìṣe mi,

Tí o sì ń wá ẹ̀ṣẹ̀ mi?+

 7 O mọ̀ pé mi ò jẹ̀bi,+

Kò sì sí ẹni tó lè gbà mí lọ́wọ́ rẹ.+

 8 Ọwọ́ rẹ lo fi mọ mí tí o sì fi dá mi,+

Àmọ́ ní báyìí, o fẹ́ pa mí run pátápátá.

 9 Jọ̀ọ́, rántí pé amọ̀ lo fi mọ mí,+

Àmọ́ ní báyìí, o mú kí n pa dà sínú erùpẹ̀.+

10 Ṣebí o dà mí jáde bíi wàrà

Tí o sì mú kí n dì bíi wàràkàṣì?

11 O fi awọ àti ẹran bò mí,

O sì fi egungun àti iṣan hun mí pọ̀.+

12 O ti fún mi ní ìyè, o sì ti fi ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ hàn sí mi;

O ti fi ìkẹ́ rẹ dáàbò bo ẹ̀mí* mi.+

13 Àmọ́ o gbèrò ní bòókẹ́lẹ́ láti ṣe àwọn nǹkan yìí.*

Mo mọ̀ pé ọ̀dọ̀ rẹ ni àwọn nǹkan yìí ti wá.

14 Tí mo bá ṣẹ̀, o máa ṣọ́ mi,+

O ò sì ní dá mi láre.

15 Tí mo bá jẹ̀bi, mo gbé!

Tí mi ò bá tiẹ̀ mọwọ́ mẹsẹ̀, mi ò lè gbé orí mi sókè,+

Torí ìtìjú àti ìyà+ ti bò mí mọ́lẹ̀.

16 Tí mo bá gbé orí mi sókè, o máa dọdẹ mi bíi ti kìnnìún,+

O sì tún máa fi agbára rẹ bá mi jà.

17 O mú àwọn ẹlẹ́rìí míì wá láti ta kò mí,

O sì túbọ̀ bínú sí mi,

Bí mo ṣe ń tinú ìnira kan bọ́ sínú ìnira míì.

18 Torí náà, kí ló dé tí o mú mi jáde látinú ikùn?+

Ó yẹ kí n ti kú kí ojú kankan tó rí mi.

19 Ṣe ni ì bá dà bíi pé mi ò gbé ayé rí;

Mi ò bá kàn ti inú ikùn lọ sí sàréè.’

20 Ṣebí àwọn ọjọ́ mi ò pọ̀?+ Kó fi mí sílẹ̀;

Kó gbé ojú rẹ̀ kúrò lọ́dọ̀ mi, kí ara lè tù mí díẹ̀*+

21 Kí n tó lọ, tí mi ò sì ní pa dà wá,+

Sí ilẹ̀ tó ṣókùnkùn biribiri,*+

22 Sí ilẹ̀ tí ìṣúdùdù rẹ̀ pọ̀ gidigidi,

Ilẹ̀ tó ṣókùnkùn biribiri, tó sì rí rúdurùdu,

Níbi tí ìmọ́lẹ̀ pàápàá ti dà bí òkùnkùn.”

11 Sófárì+ ọmọ Náámà fèsì pé:

 2 “Ṣé o ò ní gba èsì gbogbo ọ̀rọ̀ yìí ni,

Àbí ọ̀pọ̀ ọ̀rọ̀ máa mú kí ẹnì kan jàre?*

 3 Ṣé àwọn ọ̀rọ̀ rẹ tí kò nítumọ̀ máa pa àwọn èèyàn lẹ́nu mọ́?

Ṣé kò sẹ́ni tó máa bá ọ wí torí ọ̀rọ̀ ìfiniṣẹ̀sín rẹ?+

 4 Torí o sọ pé, ‘Ẹ̀kọ́ mi ò lábààwọ́n,+

Mo sì mọ́ ní ojú rẹ.’+

 5 Àmọ́ ká ní Ọlọ́run sọ̀rọ̀ ni,

Tó sì la ẹnu* rẹ̀ láti fèsì!+

 6 Ì bá sọ àwọn àṣírí ọgbọ́n fún ọ,

Torí ọgbọ́n tó gbéṣẹ́ pín sí oríṣiríṣi ọ̀nà.

O máa wá mọ̀ pé ńṣe ni Ọlọ́run yàn láti gbàgbé àwọn àṣìṣe rẹ kan.

 7 Ṣé o lè wá àwọn ohun ìjìnlẹ̀ Ọlọ́run rí,

Àbí o lè ṣàwárí gbogbo nǹkan nípa* Olódùmarè?

 8 Ó ga ju ọ̀run lọ. Kí lo lè ṣe?

Ó jìn ju Isà Òkú* lọ. Kí lo lè mọ̀?

 9 Ó gùn ju ayé lọ,

Ó sì fẹ̀ ju òkun lọ.

10 Tó bá kọjá lọ, tó sì ti ẹnì kan mọ́lé, tó wá pè é lẹ́jọ́,

Ta ló lè dá a dúró?

11 Torí ó mọ ìgbà tí àwọn èèyàn bá ń ṣẹ̀tàn.

Tó bá rí ohun tó burú, ṣé kò ní fiyè sí i?

12 Àfìgbà tí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ igbó bá bí èèyàn*

Ló máa tó yé òpònú èèyàn.

13 Ká ní o lè múra ọkàn rẹ sílẹ̀ ni,

Kí o sì na ọwọ́ rẹ sí i.

14 Bí ọwọ́ rẹ bá ń ṣe ohun tí kò dáa, mú un jìnnà,

Má sì jẹ́ kí àìṣòdodo kankan gbé inú àwọn àgọ́ rẹ.

15 Torí ìgbà yẹn ni wàá lè gbé ojú rẹ sókè láìsí àbùkù kankan;

Wàá lè dúró gbọn-in, ẹ̀rù ò sì ní bà ọ́.

16 Torí ìgbà yẹn lo máa gbàgbé ìṣòro rẹ;

O máa rántí rẹ̀ bí omi tó ti ṣàn kọjá rẹ.

17 Ayé rẹ máa mọ́lẹ̀ ju ọ̀sán gangan lọ;

Òkùnkùn rẹ̀ pàápàá máa dà bí àárọ̀.

18 Ọkàn rẹ máa balẹ̀ torí ìrètí wà,

O máa wò yí ká, o sì máa dùbúlẹ̀ láìséwu.

19 Wàá dùbúlẹ̀, ẹnì kankan ò sì ní dẹ́rù bà ọ́,

Ọ̀pọ̀ èèyàn á sì máa wá ojúure rẹ.

20 Àmọ́ ojú àwọn ẹni burúkú ò ní ríran mọ́;

Wọn ò sì ní ríbi sá lọ,

Ikú* nìkan ló sì máa jẹ́ ìrètí wọn.”+

12 Jóòbù wá fèsì pé:

 2 “Ó dájú pé ẹ̀yin lẹ ní ìmọ̀,*

Ọgbọ́n sì máa bá yín kú!

 3 Àmọ́ èmi náà ní òye.*

Mi ò kéré sí yín,

Ta ni ò mọ àwọn nǹkan yìí?

 4 Mo wá di ẹni tí àwọn ọ̀rẹ́ fi ń ṣe ẹlẹ́yà,+

Ẹni tó ń ké pe Ọlọ́run pé kó dáhùn.+

Ẹni tó jẹ́ olódodo àti aláìlẹ́bi ni wọ́n fi ń ṣe ẹlẹ́yà.

 5 Ẹni tí ara máa ń tù kórìíra àjálù,

Ó rò pé àwọn tí ẹsẹ̀ wọn ò múlẹ̀* nìkan ló máa ń dé bá.

 6 Àgọ́ àwọn olè wà ní àlàáfíà,+

Àwọn tó sì ń mú Ọlọ́run bínú wà láìséwu,+

Àwọn tí ọlọ́run wọn wà ní ọwọ́ wọn.

 7 Àmọ́ jọ̀ọ́, bi àwọn ẹranko, wọ́n á sì kọ́ ọ;

Àti àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run, wọ́n á sì sọ fún ọ.

 8 Tàbí kí o fiyè sí ayé,* ó sì máa kọ́ ọ;

Àwọn ẹja inú òkun sì máa kéde rẹ̀ fún ọ.

 9 Èwo nínú gbogbo àwọn yìí ni kò mọ̀

Pé ọwọ́ Jèhófà ló ṣe èyí?

10 Ọwọ́ rẹ̀ ni ẹ̀mí gbogbo ohun alààyè* wà

Àti ẹ̀mí* gbogbo èèyàn.*+

11 Ṣebí etí máa ń dán ọ̀rọ̀ wò,

Bí ahọ́n* ṣe ń tọ́ oúnjẹ wò?+

12 Ṣebí ọ̀dọ̀ àwọn àgbà+ la ti ń rí ọgbọ́n,

Ṣebí ẹ̀mí gígùn sì ń mú kéèyàn ní òye?

13 Ọgbọ́n àti agbára ńlá wà lọ́dọ̀ rẹ̀;+

Ó ní ìmọ̀ràn àti òye.+

14 Tó bá ya nǹkan lulẹ̀, kò ṣeé tún kọ́;+

Tó bá ti nǹkan pa, èèyàn kankan ò lè ṣí i.

15 Tó bá dá omi dúró, ohun gbogbo á gbẹ;+

Tó bá sì rán an jáde, á bo ayé.+

16 Ọ̀dọ̀ rẹ̀ ni agbára àti ọgbọ́n tó gbéṣẹ́ wà;+

Òun ló ni ẹni tó ń ṣìnà àti ẹni tó ń kóni ṣìnà;

17 Ó ń mú kí àwọn agbani-nímọ̀ràn lọ láìwọ bàtà,*

Ó ń sọ àwọn adájọ́ di òmùgọ̀.+

18 Ó ń tú ìdè tí àwọn ọba fi deni,+

Ó sì ń de àmùrè mọ́ ìgbáròkó wọn.

19 Ó ń mú kí àwọn àlùfáà rìn láìwọ bàtà,+

Ó sì ń gbàjọba lọ́wọ́ àwọn tí wọ́n fìdí múlẹ̀ gbọn-in nípò agbára;+

20 Ó ń pa àwọn agbani-nímọ̀ràn tí wọ́n fọkàn tán lẹ́nu mọ́,

Ó sì ń gba làákàyè àwọn àgbà ọkùnrin;*

21 Ó ń rọ̀jò àbùkù sórí àwọn èèyàn pàtàkì,+

Ó sì ń mú kó rẹ àwọn alágbára;*

22 Ó ń tú àwọn ohun tó jinlẹ̀ síta látinú òkùnkùn,+

Ó sì ń tan ìmọ́lẹ̀ sí òkùnkùn biribiri;

23 Ó ń mú kí àwọn orílẹ̀-èdè di ńlá, kó lè pa wọ́n run;

Ó ń mú kí àwọn orílẹ̀-èdè tóbi sí i, kó lè kó wọn lọ sí ìgbèkùn.

24 Ó ń gba òye* àwọn olórí àwọn èèyàn,

Ó sì ń mú kí wọ́n rìn kiri ní ilẹ̀ tó ti di ahoro, tí kò sì lójú ọ̀nà.+

25 Wọ́n ń táràrà nínú òkùnkùn,+ níbi tí kò ti sí ìmọ́lẹ̀;

Ó ń mú kí wọ́n máa rìn gbéregbère bí ọ̀mùtípara.+

13 “Àní ojú mi ti rí gbogbo èyí,

Etí mi ti gbọ́, ó sì ti yé mi.

 2 Ohun tí ẹ mọ̀ ni èmi náà mọ̀;

Mi ò kéré sí yín.

 3 Ní tèmi, màá kúkú bá Olódùmarè fúnra rẹ̀ sọ̀rọ̀;

Ọlọ́run ni mo fẹ́ ro ẹjọ́ mi fún.+

 4 Ẹ̀ ń fi irọ́ bà mí lórúkọ jẹ́;

Oníṣègùn tí kò wúlò ni gbogbo yín.+

 5 Ká ní ẹ lè dákẹ́ láìsọ nǹkan kan ni,

Ìyẹn ì bá fi hàn pé ẹ jẹ́ ọlọ́gbọ́n!+

 6 Ẹ jọ̀ọ́, ẹ tẹ́tí gbọ́ àlàyé mi,

Kí ẹ sì fiyè sí àrọwà ètè mi.

 7 Ṣé ẹ máa sọ̀rọ̀ tí kò tọ́ láti gbèjà Ọlọ́run,

Ṣé ẹ fẹ́ sọ̀rọ̀ ẹ̀tàn láti gbè é lẹ́yìn?

 8 Ṣé ẹ máa gbè sẹ́yìn rẹ̀,*

Ṣé ẹ fẹ́ máa gbèjà Ọlọ́run tòótọ́ ni?

 9 Tó bá yẹ̀ yín wò, ṣé ibi tó dáa ló máa já sí?+

Àbí ẹ máa tàn án jẹ bí ẹ ṣe máa tan ẹni kíkú?

10 Tí ẹ bá gbìyànjú láti ṣe ojúsàájú níkọ̀kọ̀,+

Ó dájú pé ó máa bá yín wí.

11 Ṣé iyì rẹ̀ pàápàá kò ní kó jìnnìjìnnì bá yín,

Ṣé ẹ̀rù rẹ̀ kò sì ní bà yín?

12 Àwọn ọ̀rọ̀ ọgbọ́n* yín jẹ́ òwe tó dà bí eérú;

Àwọn ohun tí ẹ fi ń gbèjà ara yín* ò lágbára, wọ́n dà bí ohun tí wọ́n fi amọ̀ ṣe.

13 Ẹ dákẹ́ níwájú mi, kí n lè sọ̀rọ̀.

Kí ohunkóhun tó bá wá fẹ́ ṣẹlẹ̀ sí mi ṣẹlẹ̀!

14 Kí ló dé tí mo fi ara mi sínú ewu,*

Tí mo sì fi ẹ̀mí* mi sọ́wọ́ mi?

15 Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ó lè pa mí, màá ṣì dúró;+

Màá ro ẹjọ́ mi* níwájú rẹ̀.

16 Ó máa wá di ìgbàlà mi,+

Torí ẹni tí kò mọ Ọlọ́run* kò lè wá síwájú rẹ̀.+

17 Ẹ fetí sílẹ̀ dáadáa sí ọ̀rọ̀ mi;

Ẹ fiyè sí ohun tí mo fẹ́ sọ.

18 Ẹ wò ó, mo ti múra ẹjọ́ mi sílẹ̀ báyìí;

Mo mọ̀ pé èmi ni mo jàre.

19 Ta ló máa bá mi fà á?

Màá kú tí mo bá dákẹ́!*

20 Ohun méjì péré ni kí o ṣe fún mi, ìwọ Ọlọ́run,*

Kí n má bàa fi ara mi pa mọ́ níwájú rẹ:

21 Gbé ọwọ́ rẹ tó wúwo jìnnà réré sí mi,

Má sì jẹ́ kí ẹ̀rù rẹ kó jìnnìjìnnì bá mi.+

22 Nínú kí o pè, kí n sì dá ọ lóhùn,

Tàbí kí o jẹ́ kí n sọ̀rọ̀, kí o sì dá mi lóhùn.

23 Ẹ̀ṣẹ̀ wo ni mo ṣẹ̀, kí sì ni àṣìṣe mi?

Jẹ́ kí n mọ ìṣìnà mi àti ẹ̀ṣẹ̀ mi.

24 Kí ló dé tí o fi ojú rẹ pa mọ́,+

Tí o sì kà mí sí ọ̀tá rẹ?+

25 Ṣé o máa fẹ́ dẹ́rù ba ewé tí afẹ́fẹ́ ń gbé kiri ni,

Àbí o fẹ́ máa sáré lé àgékù pòròpórò tó ti gbẹ?

26 Torí ò ń fẹ̀sùn tó le kàn mí, o sì ń kọ ọ́ sílẹ̀ ṣáá,

O sì mú kí n jìyà àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tí mo dá nígbà tí mo ṣì kéré.

27 O ti ẹsẹ̀ mi mọ́ inú àbà,

Ò ń ṣọ́ gbogbo ọ̀nà mi lójú méjèèjì,

O sì ń wá ipasẹ̀ mi jáde lọ́kọ̀ọ̀kan.

28 Torí náà, èèyàn* ń jẹrà bí ohun tó ti rà,

Bí aṣọ tí òólá* ti jẹ.

14 “Èèyàn tí obìnrin bí,

Ọlọ́jọ́ kúkúrú ni,+ wàhálà* rẹ̀ sì máa ń pọ̀ gan-an.+

 2 Ó jáde wá bí ìtànná, ó sì rọ dà nù;*+

Ó ń sá lọ bí òjìji, ó sì pòórá.+

 3 Àní, o ti tẹjú mọ́ ọn,

O sì ti bá a* ṣe ẹjọ́.+

 4 Ta ló lè mú ẹni tó mọ́ jáde látinú ẹni tí kò mọ́?+

Kò sẹ́ni tó lè ṣe é!

 5 Tí a bá ti pinnu àwọn ọjọ́ rẹ̀,

Iye oṣù rẹ̀ wà lọ́wọ́ rẹ;

O ti pààlà fún un, kó má bàa kọjá rẹ̀.+

 6 Gbé ojú rẹ kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀ kó lè sinmi,

Títí ó fi máa lo ọjọ́ rẹ̀ tán+ bí alágbàṣe.

 7 Torí ìrètí wà fún igi pàápàá.

Tí wọ́n bá gé e lulẹ̀, ó máa hù pa dà,

Àwọn ẹ̀ka rẹ̀ á sì máa dàgbà.

 8 Tí gbòǹgbò rẹ̀ bá gbó sínú ilẹ̀,

Tí kùkùté rẹ̀ sì kú sínú iyẹ̀pẹ̀,

 9 Ó máa hù tó bá gbúròó omi;

Ó sì máa yọ ẹ̀ka bí ewéko tó ṣẹ̀ṣẹ̀ hù.

10 Àmọ́ èèyàn kú, ó sì wà nílẹ̀ láìlágbára;

Tí èèyàn bá gbẹ́mìí mì, ibo ló wà?+

11 Omi dàwátì nínú òkun,

Odò ń fà, ó sì gbẹ táútáú.

12 Bẹ́ẹ̀ ni èèyàn ń dùbúlẹ̀, kì í sì í dìde.+

Títí ọ̀run kò fi ní sí mọ́, wọn ò ní jí,

Bẹ́ẹ̀ ni a ò ní jí wọn lójú oorun.+

13 Ká ní o lè fi mí pa mọ́ sínú Isà Òkú* ni,+

Kí o fi mí pa mọ́ títí ìbínú rẹ fi máa kọjá,

Kí o yan àkókò kan sílẹ̀ fún mi, kí o sì rántí mi!+

14 Tí èèyàn bá kú, ṣé ó tún lè wà láàyè?+

Màá dúró jálẹ̀ gbogbo ọjọ́ tó pọn dandan pé kí n lò,

Títí ìtura mi fi máa dé. +

15 O máa pè, màá sì dá ọ lóhùn.+

Ó máa wù ọ́ gan-an láti rí* iṣẹ́ ọwọ́ rẹ.

16 Àmọ́ ní báyìí, ò ń ka gbogbo ìṣísẹ̀ mi ṣáá;

Ẹ̀ṣẹ̀ mi nìkan lò ń ṣọ́.

17 O sé ẹ̀ṣẹ̀ mi mọ́ inú àpò,

O sì fi àtè lẹ àṣìṣe mi pa.

18 Bí òkè ṣe máa ń ṣubú, tó sì ń fọ́ sí wẹ́wẹ́,

Tí àpáta sì ń ṣí kúrò ní àyè rẹ̀,

19 Bí omi ṣe ń mú kí òkúta yìnrìn,

Tí ọ̀gbàrá rẹ̀ sì ń wọ́ iyẹ̀pẹ̀ ilẹ̀.

Bẹ́ẹ̀ lo ṣe sọ ìrètí ẹni kíkú dòfo.

20 Ò ń borí rẹ̀ títí ó fi ṣègbé;+

O yí ìrísí rẹ̀ pa dà, o sì ní kó máa lọ.

21 A bọlá fún àwọn ọmọ rẹ̀, àmọ́ kò mọ̀;

Wọ́n di ẹni tí kò ní láárí, àmọ́ kò mọ̀.+

22 Ìgbà tó ṣì jẹ́ ẹlẹ́ran ara nìkan ló mọ̀ pé òun ń jẹ̀rora;

Ìgbà tí ó* ṣì wà láàyè nìkan ló ń ṣọ̀fọ̀.”

15 Élífásì+ ará Témánì fèsì pé:

 2 “Ṣé ọlọ́gbọ́n èèyàn máa fi ọ̀rọ̀ tí kò nítumọ̀* fèsì ni,

Àbí ó máa fi atẹ́gùn ìlà oòrùn kún inú rẹ̀?

 3 Fífi ọ̀rọ̀ lásán báni wí kò wúlò,

Ọ̀rọ̀ ẹnu lásán ò sì ṣàǹfààní.

 4 Torí o ti sọ ìbẹ̀rù Ọlọ́run di ahẹrẹpẹ,

O sì mú kí ìrònú nípa Ọlọ́run dín kù.

 5 Àṣìṣe rẹ ló ń mú kí o máa sọ̀rọ̀ báyìí,*

O sì yàn láti sọ̀rọ̀ àrékérekè.

 6 Ẹnu ara rẹ ló ń dá ọ lẹ́bi, kì í ṣe èmi;

Ètè ìwọ fúnra rẹ sì jẹ́rìí ta kò ọ́.+

 7 Ṣé ìwọ ni èèyàn tí wọ́n máa kọ́kọ́ bí,

Àbí wọ́n ti bí ọ ṣáájú àwọn òkè?

 8 Ṣé ò ń fetí sí ọ̀rọ̀ àṣírí Ọlọ́run,

Àbí ìwọ nìkan lo rò pé o gbọ́n?

 9 Kí lo mọ̀ tí a kò mọ̀?+

Kí ló yé ọ tí kò yé wa?

10 Àwọn tó ní ewú lórí àtàwọn àgbàlagbà wà láàárín wa,+

Àwọn tó dàgbà ju bàbá rẹ lọ fíìfíì.

11 Ṣé ìtùnú Ọlọ́run kò tó ọ ni,

Àbí ọ̀rọ̀ jẹ́ẹ́jẹ́ẹ́ tí a bá ọ sọ?

12 Kí ló dé tí ọkàn rẹ ń gbé ọ lọ,

Kí ló sì dé tí ìbínú ń kọ mànà lójú rẹ?

13 Torí o ti mú kí ẹ̀mí rẹ ta ko Ọlọ́run fúnra rẹ̀,

O sì jẹ́ kí irú àwọn ọ̀rọ̀ yẹn ti ẹnu rẹ jáde.

14 Kí ni ẹni kíkú jẹ́ tó fi máa mọ́,

Tàbí ẹnikẹ́ni tí obìnrin bí tó fi máa jẹ́ olódodo?+

15 Wò ó! Kò ní ìgbàgbọ́ nínú àwọn ẹni mímọ́ rẹ̀,

Àwọn ọ̀run pàápàá kò mọ́ ní ojú rẹ̀.+

16 Mélòómélòó wá ni ẹni tó jẹ́ ẹni ìríra àti oníwà ìbàjẹ́,+

Ẹni tó ń mu àìṣòdodo bí ẹni mu omi!

17 Màá sọ fún ọ; fetí sí mi!

Màá ròyìn ohun tí mo rí,

18 Ohun tí àwọn amòye ròyìn, bí wọ́n ṣe gbọ́ ọ lẹ́nu àwọn bàbá wọn,+

Àwọn ohun tí wọn ò fi pa mọ́.

19 Àwọn nìkan la fún ní ilẹ̀ náà,

Àjèjì kankan ò sì gba àárín wọn.

20 Ẹni burúkú ń joró ní gbogbo ọjọ́ rẹ̀,

Jálẹ̀ gbogbo ọdún tí a yà sọ́tọ̀ fún oníwà ìkà.

21 Etí rẹ̀ ń gbọ́ àwọn ìró tó ń bani lẹ́rù;+

Nígbà àlàáfíà, àwọn tó ń kóni lẹ́rù dìde sí i.

22 Kò gbà gbọ́ pé òun máa bọ́ lọ́wọ́ òkùnkùn;+

A fi í pa mọ́ de idà.

23 Ó ń wá oúnjẹ* kiri, ibo ló wà?

Ó mọ̀ dáadáa pé ọjọ́ òkùnkùn ti sún mọ́lé.

24 Ìdààmú àti ìrora ń kó jìnnìjìnnì bá a;

Wọ́n borí rẹ̀ bí ọba tó múra tán láti jagun.

25 Torí ó gbé ọwọ́ rẹ̀ lòdì sí Ọlọ́run fúnra rẹ̀,

Ó sì fẹ́ ta ko* Olódùmarè;

26 Ó fi orí kunkun pa kuuru mọ́ ọn,

Pẹ̀lú apata rẹ̀ tó nípọn tó sì lágbára;*

27 Ọ̀rá mú kí ojú rẹ sanra,

Ọ̀rá sì mú kí ìbàdí rẹ̀ yọ;

28 Ó ń gbé ní àwọn ìlú tó máa pa run,

Nínú àwọn ilé tí ẹnì kankan ò ní gbé,

Tó máa di òkìtì òkúta.

29 Kò ní di ọlọ́rọ̀, ọlá rẹ̀ kò sì ní pọ̀ sí i,

Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ohun ìní rẹ̀ kò ní tàn ká ilẹ̀ náà.

30 Kò ní bọ́ lọ́wọ́ òkùnkùn;

Ọwọ́ iná máa mú kí ẹ̀ka igi rẹ̀ gbẹ,*

Atẹ́gùn líle láti ẹnu Ọlọ́run* sì máa mú kó pa rẹ́.+

31 Kó má yà bàrá, kó má sì gbẹ́kẹ̀ lé ohun tí kò ní láárí,

Torí ohun tí kò ní láárí ló máa gbà pa dà;

32 Ó máa ṣẹlẹ̀ ṣáájú ọjọ́ rẹ̀,

Àwọn ẹ̀ka rẹ̀ ò sì ní gbèrú rárá.+

33 Ó máa dà bí èso àjàrà tó gbọn àwọn èso rẹ̀ tí kò tíì pọ́n dà nù

Àti bí igi ólífì tó gbọn ìtànná rẹ̀ dà nù.

34 Torí àpéjọ àwọn tí kò mọ Ọlọ́run* kò lè méso jáde,+

Iná á sì jó àwọn àgọ́ àbẹ̀tẹ́lẹ̀ run.

35 Wọ́n lóyún ìjàngbọ̀n, wọ́n sì bí ohun tó burú,

Ẹ̀tàn ń ti inú ikùn wọn jáde.”

16 Jóòbù fèsì pé:

 2 “Mo ti gbọ́ ọ̀pọ̀ nǹkan báyìí rí.

Olùtùnú tó ń dani láàmú ni gbogbo yín!+

 3 Ṣé àwọn ọ̀rọ̀ asán* lópin ni?

Kí ló ń bí ẹ nínú tí o fi ń fèsì báyìí?

 4 Èmi náà lè sọ̀rọ̀ bíi tiyín.

Ká ní ẹ̀yin lẹ wà ní ipò tí mo wà,*

Mo lè sọ̀rọ̀ sí yín, tó máa mú kí ẹ ronú,

Mo sì lè mi orí sí yín.+

 5 Kàkà bẹ́ẹ̀, màá fi ọ̀rọ̀ ẹnu mi fún yín lókun,

Ìtùnú ètè mi á sì mú kí ara tù yín.+

 6 Tí mo bá sọ̀rọ̀, kò dín ìrora mi kù,+

Tí mo bá sì dákẹ́, mélòó ló máa dín kù nínú ìrora mi?

 7 Àmọ́, ó ti tán mi lókun báyìí;+

Ó ti run gbogbo agbo ilé mi.*

 8 O tún gbá mi mú, ó sì ti jẹ́rìí sí i,

Débi pé ara mi tó rù kan eegun dìde, ó sì jẹ́rìí níṣojú mi.

 9 Ìbínú rẹ̀ ti fà mí ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ, ó sì ń dì mí sínú.+

Ó ń wa eyín pọ̀ sí mi.

Ọ̀tá mi ń fi ojú rẹ̀ gún mi lára.+

10 Wọ́n ti la ẹnu wọn gbàù sí mi,+

Tẹ̀gàntẹ̀gàn ni wọ́n sì gbá mi ní ẹ̀rẹ̀kẹ́,

Wọ́n kóra jọ rẹpẹtẹ láti ta kò mí.+

11 Ọlọ́run fi mí lé àwọn ọ̀dọ́kùnrin lọ́wọ́,

Ó sì tì mí sọ́wọ́ àwọn ẹni burúkú.+

12 Wàhálà kankan ò bá mi, àmọ́ ó fọ́ mi sí wẹ́wẹ́;+

Ó rá mi mú ní ẹ̀yìn ọrùn, ó sì fọ́ mi túútúú;

Èmi ló dájú sọ.

13 Àwọn tafàtafà rẹ̀ yí mi ká;+

Ó gún àwọn kíndìnrín mi,+ àánú ò sì ṣe é;

Ó da òróòro mi sórí ilẹ̀.

14 Ó ń dá ihò sí mi lára, ọ̀kan tẹ̀ lé òmíràn;

Ó pa kuuru mọ́ mi bíi jagunjagun.

15 Mo ti rán aṣọ ọ̀fọ̀* pọ̀ láti fi bo ara mi,+

Mo sì ti bo iyì* mi mọ́ inú iyẹ̀pẹ̀.+

16 Ojú mi ti pọ́n torí mò ń sunkún,+

Òkùnkùn biribiri* sì wà ní ìpéǹpéjú mi,

17 Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ọwọ́ mi ò hùwà ipá kankan,

Àdúrà mi sì mọ́.

18 Ìwọ ilẹ̀, má bo ẹ̀jẹ̀ mi!+

Má sì jẹ́ kí igbe mi rí ibi ìsinmi kankan!

19 Kódà ní báyìí, ẹlẹ́rìí mi wà ní ọ̀run;

Ẹni tó lè jẹ́rìí sí mi wà ní ibi tó ga.

20 Àwọn ọ̀rẹ́ mi fi mí ṣe ẹlẹ́yà,+

Bí mo ṣe ń da omi lójú sí Ọlọ́run.*+

21 Kí ẹnì kan gbọ́ ẹjọ́ èèyàn àti Ọlọ́run

Bí èèyàn ṣe ń gbọ́ ẹjọ́ ẹnì kan àti ẹnì kejì rẹ̀.+

22 Torí àwọn ọdún tó ń bọ̀ kéré,

Màá sì gba ọ̀nà ibi tí mi ò ti ní pa dà wá mọ́.+

17 “Ìbànújẹ́ ti bá ẹ̀mí mi, àwọn ọjọ́ mi ti dópin;

Itẹ́ òkú ń retí mi.+

 2 Àwọn tó ń fini ṣe yẹ̀yẹ́ yí mi ká,+

Àfi kí ojú mi máa wo* ìwà ọ̀tẹ̀ wọn.

 3 Jọ̀ọ́, gba ohun tí mo fi ṣe ìdúró, kí o sì tọ́jú rẹ̀ sọ́dọ̀ rẹ.

Ta ló tún máa bọ̀ mí lọ́wọ́, tó sì máa dúró fún mi?+

 4 Torí o ò jẹ́ kí ọkàn wọn ní òye;+

Ìdí nìyẹn tí o kò fi gbé wọn ga.

 5 Ó lè fẹ́ kí òun àti àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ pín in,

Síbẹ̀, ojú àwọn ọmọ rẹ̀ ń ṣú.

 6 Ó ti sọ mí di ẹni ẹ̀gàn* láàárín àwọn èèyàn,+

Tí mo fi di ẹni tí wọ́n ń tutọ́ sí lójú.+

 7 Ìrora ti sọ ojú mi di bàìbàì,+

Òjìji sì ni gbogbo apá àti ẹsẹ̀ mi.

 8 Àwọn olóòótọ́ ń wo èyí tìyanutìyanu,

Ọkàn aláìṣẹ̀ ò sì balẹ̀ torí ẹni tí kò mọ Ọlọ́run.*

 9 Olódodo kò fi ọ̀nà rẹ̀ sílẹ̀ rárá,+

Ẹni tí ọwọ́ rẹ̀ mọ́ sì ń lágbára sí i.+

10 Àmọ́ gbogbo yín tún lè wá máa ro ẹjọ́ yín,

Torí mi ò rí ọlọ́gbọ́n kankan nínú yín.+

11 Àwọn ọjọ́ mi ti dópin;+

Àwọn ohun tí mo fẹ́ ṣe, àwọn ohun tí ọkàn mi fẹ́, ti já sí asán.+

12 Wọ́n ń sọ òru di ọ̀sán,

Wọ́n ń sọ pé, ‘Ó ní láti jẹ́ pé ìmọ́lẹ̀ wà nítòsí torí òkùnkùn ṣú.’

13 Tí mo bá dúró, Isà Òkú* máa di ilé mi;+

Màá tẹ́ ibùsùn mi sínú òkùnkùn.+

14 Màá ké pe ihò*+ pé, ‘Ìwọ ni bàbá mi!’

Àti ìdin pé, ‘Ìyá mi àti arábìnrin mi!’

15 Ibo wá ni ìrètí mi+ wà?

Ta ló lè bá mi rí ìrètí?

16 Ó* máa sọ̀ kalẹ̀ lọ sí àwọn ẹnubodè Isà Òkú* tí wọ́n tì pa

Tí gbogbo wa bá jọ sọ̀ kalẹ̀ lọ sínú iyẹ̀pẹ̀.”+

18 Bílídádì+ ọmọ Ṣúáhì fèsì pé:

 2 “Ìgbà wo lẹ ò ní sọ̀rọ̀ báyìí mọ́?

Ẹ lo òye, ká lè wá sọ̀rọ̀.

 3 Kí ló dé tí ẹ̀ ń fojú ẹranko wò wá,+

Tí ẹ sì kà wá sí òpònú?*

 4 Tí o bá tiẹ̀ fa ara* rẹ ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ torí inú tó ń bí ọ,

Ṣé a máa pa ayé tì nítorí rẹ ni,

Àbí àpáta máa ṣí kúrò ní àyè rẹ̀?

 5 Àní, a máa pa iná ẹni burúkú,

Ọwọ́ iná rẹ̀ kò sì ní tàn.+

 6 Ó dájú pé ìmọ́lẹ̀ inú àgọ́ rẹ̀ máa di òkùnkùn,

A sì máa fẹ́ fìtílà tó wà lórí rẹ̀ pa.

 7 Ìrìn tó ń fi tagbáratagbára rìn dín kù,

Ìmọ̀ràn ara rẹ̀ sì máa gbé e ṣubú.+

 8 Torí ẹsẹ̀ rẹ̀ máa mú un wọnú àwọ̀n,

Ó sì máa rìn gbéregbère wọnú àwọn okùn rẹ̀.

 9 Pańpẹ́ máa mú un ní gìgísẹ̀;

Ìdẹkùn á sì mú un.+

10 Okùn kan ti wà nípamọ́ dè é lórí ilẹ̀,

Pańpẹ́ sì wà lójú ọ̀nà rẹ̀.

11 Jìnnìjìnnì bò ó yí ká,+

Ó sì ń sá tẹ̀ lé e ní ẹsẹ̀ rẹ̀.

12 Okun tán nínú rẹ̀,

Àjálù+ sì máa mú kó ta gọ̀ọ́gọ̀ọ́.*

13 Awọ ara rẹ̀ jẹ dà nù;

Àìsàn gbẹ̀mí-gbẹ̀mí tó lágbára jù* jẹ apá àti ẹsẹ̀ rẹ̀ run.

14 Wọ́n fà á kúrò nínú àgọ́ rẹ̀ tí ààbò wà,+

Lọ sọ́dọ̀ ọba ẹ̀rù jẹ̀jẹ̀.*

15 Àwọn àjèjì* á máa gbé inú àgọ́ rẹ̀;

A máa fọ́n imí ọjọ́ sórí ilé rẹ̀.+

16 Gbòǹgbò rẹ̀ máa gbẹ lábẹ́ rẹ̀,

Àwọn ẹ̀ka rẹ̀ sì máa rọ lórí rẹ̀.

17 Wọn ò ní rántí rẹ̀ mọ́ ní ayé,

Wọn ò sì ní mọ orúkọ rẹ̀* ní àdúgbò.

18 Wọ́n máa lé e kúrò nínú ìmọ́lẹ̀ sínú òkùnkùn,

Wọ́n sì máa lé e kúrò ní ilẹ̀ tó ń méso jáde.

19 Kò ní ní ọmọ àti àtọmọdọ́mọ láàárín àwọn èèyàn rẹ̀,

Kò sì ní sí ẹni tó máa yè bọ́ níbi tó ń gbé.*

20 Tí ọjọ́ rẹ̀ bá dé, àwọn èèyàn tó wà ní Ìwọ̀ Oòrùn máa bẹ̀rù,

Jìnnìjìnnì sì máa bo àwọn èèyàn tó wà ní Ìlà Oòrùn.

21 Ohun tó máa ń ṣẹlẹ̀ sí àgọ́ ẹni burúkú nìyí

Àti ibùgbé ẹni tí kò mọ Ọlọ́run.”

19 Jóòbù fèsì pé:

 2 “Ìgbà wo lẹ ò ní mú ọkàn mi* bínú mọ́,+

Tí ẹ ò ní fi ọ̀rọ̀+ fọ́ mi sí wẹ́wẹ́?

 3 Ìgbà mẹ́wàá yìí lẹ ti bá mi wí;*

Ojú ò tì yín láti fọwọ́ tó le mú mi.+

 4 Tí mo bá tiẹ̀ ṣàṣìṣe,

Èmi ni mo ni àṣìṣe náà.

 5 Tí ẹ bá ṣì ń gbé ara yín ga jù mí lọ,

Tí ẹ̀ ń sọ pé ó tọ́ láti fi mí ṣẹlẹ́yà,

 6 Nígbà náà, kí ẹ mọ̀ pé Ọlọ́run ló ṣì mí lọ́nà,

Ó sì ti fi àwọ̀n tó fi ń dọdẹ mú mi.

 7 Wò ó! Mò ń ké ṣáá pé, ‘Ìwà ipá!’ àmọ́ kò sẹ́ni tó dáhùn;+

Mò ń kígbe ṣáá pé mo nílò ìrànlọ́wọ́, àmọ́ kò sí ìdájọ́ òdodo.+

 8 Ó ti fi ògiri olókùúta dí ọ̀nà mi, mi ò sì lè kọjá;

Ó ti fi òkùnkùn+ bo àwọn òpópónà mi.

 9 Ó ti bọ́ ògo mi kúrò lára mi,

Ó sì ti ṣí adé kúrò lórí mi.

10 Ó wó mi lulẹ̀ yí ká títí mo fi ṣègbé;

Ó sì fa ìrètí mi tu bí igi.

11 Ó bínú sí mi gidigidi,

Ó sì kà mí sí ọ̀tá rẹ̀.+

12 Àwọn ọmọ ogun rẹ̀ kóra jọ, wọ́n sì gbéjà kò mí,

Wọ́n pàgọ́ yí ibùdó mi ká.

13 Ó ti lé àwọn arákùnrin mi jìnnà réré sí mi,

Àwọn tó sì mọ̀ mí ti kúrò lọ́dọ̀ mi.+

14 Àwọn ọ̀rẹ́ mi tímọ́tímọ́* ti lọ,

Àwọn tí mo sì mọ̀ dáadáa ti gbàgbé mi.+

15 Mo ti di àjèjì sí àwọn àlejò inú ilé mi+ àti àwọn ẹrúbìnrin mi;

Ọmọ ilẹ̀ òkèèrè ni mo jẹ́ lójú wọn.

16 Mo pe ìránṣẹ́ mi, àmọ́ kò dáhùn;

Ẹnu mi ni mo fi bẹ̀ ẹ́ pé kó ṣàánú mi.

17 Kódà ìyàwó mi ti kórìíra èémí mi gidigidi,+

Mo sì ti di òórùn burúkú sí àwọn arákùnrin mi.*

18 Àwọn ọmọdé pàápàá fojú àbùkù wò mí;

Tí mo bá dìde, wọ́n á bẹ̀rẹ̀ sí í fi mí ṣe yẹ̀yẹ́.

19 Gbogbo ọ̀rẹ́ mi tímọ́tímọ́ kórìíra mi,+

Àwọn tí mo sì nífẹ̀ẹ́ ti kẹ̀yìn sí mi.+

20 Egungun mi lẹ̀ mọ́ awọ ara mi àti ẹran ara mi,+

Awọ eyín mi ni mo sì fi yè bọ́.

21 Ẹ ṣàánú mi, ẹ̀yin ọ̀rẹ́ mi, ẹ ṣàánú mi,

Torí ọwọ́ Ọlọ́run fúnra rẹ̀ ti kàn mí.+

22 Kí ló dé tí ẹ̀ ń ṣe inúnibíni sí mi bíi ti Ọlọ́run,+

Tí ẹ̀ ń gbéjà kò mí láìdáwọ́ dúró?*+

23 Ká ní wọ́n kọ ọ̀rọ̀ mi sílẹ̀ ni,

Ká ní wọ́n lè kọ ọ́ sínú ìwé!

24 Ká ní wọ́n lè fi kálàmù irin àti òjé gbẹ́ ẹ

Sára àpáta, kó lè wà níbẹ̀ títí láé!

25 Torí ó dá mi lójú pé olùràpadà*+ mi wà láàyè;

Ó máa wá tó bá yá, ó sì máa dìde lórí ayé.*

26 Tí awọ ara mi bá ti ṣí kúrò,*

Tí mo ṣì ní ẹran lára, màá rí Ọlọ́run,

27 Ẹni tí màá rí fúnra mi,

Ẹni tí màá fi ojú ara mi rí, kì í ṣe ojú ẹlòmíì.+

Àmọ́ nínú lọ́hùn-ún, ó ti sú mi pátápátá!*

28 Torí ẹ sọ pé, ‘Báwo la ṣe ń ṣe inúnibíni sí i?’+

Nígbà tó jẹ́ pé èmi ni orísun ìṣòro náà.

29 Kí ẹ̀yin fúnra yín bẹ̀rù idà,+

Torí idà ń mú ìyà ẹ̀ṣẹ̀ wá;

Ó yẹ kí ẹ mọ̀ pé adájọ́ wà.”+

20 Sófárì+ ọmọ Náámà fèsì pé:

 2 “Ìdí nìyí tí àwọn èrò tó ń dà mí láàmú fi mú kí n fèsì,

Nítorí ìdààmú tó bá mi.

 3 Mo ti gbọ́ ìbáwí tí o fi bú mi;

Òye mi* sì mú kí n fèsì.

 4 Ó dájú pé o gbọ́dọ̀ ti mọ èyí tipẹ́,

Torí ó ti wà bẹ́ẹ̀ látìgbà tí èèyàn* ti wà ní ayé,+

 5 Pé igbe ayọ̀ ẹni burúkú kì í pẹ́

Àti pé ìgbà díẹ̀ ni inú ẹni tí kò mọ Ọlọ́run* fi máa ń dùn.+

 6 Bí títóbi rẹ̀ tiẹ̀ ga dé ọ̀run,

Tí orí rẹ̀ sì kan sánmà,

 7 Ó máa ṣègbé títí láé bí ìgbẹ́ òun fúnra rẹ̀;

Àwọn tó ti ń rí i máa sọ pé, ‘Ibo ló wà?’

 8 Ó máa fò lọ bí àlá, wọn ò sì ní rí i;

A máa lé e lọ, bí ìran òru.

 9 Ojú tó fìgbà kan rí i kò ní rí i mọ́,

Àyè rẹ̀ ò sì ní rí i mọ́.+

10 Àwọn ọmọ rẹ̀ máa wá ojúure lọ́dọ̀ aláìní,

Ọwọ́ ara rẹ̀ sì máa dá ọrọ̀ rẹ̀ pa dà.+

11 Okun ìgbà èwe kún inú àwọn egungun rẹ̀,

Àmọ́, ó* máa bá a dùbúlẹ̀ sínú erùpẹ̀ lásán.

12 Tí ohun tó burú bá dùn lẹ́nu rẹ̀,

Tó bá fi pa mọ́ sábẹ́ ahọ́n rẹ̀,

13 Tó bá ń gbádùn rẹ̀, tí kò sì gbé e mì,

Àmọ́ tó ṣì fi í sẹ́nu,

14 Oúnjẹ rẹ̀ máa kan nínú rẹ̀;

Ó máa dà bí oró* ṣèbé nínú rẹ̀.

15 Ó ti gbé ọrọ̀ mì, àmọ́ ó máa pọ̀ ọ́;

Ọlọ́run máa kó o jáde nínú ikùn rẹ̀.

16 Ó máa fa oró ṣèbé mu;

Eyín* paramọ́lẹ̀ máa pa á.

17 Kò ní rí odò tó ń ṣàn láé,

Ọ̀gbàrá oyin àti bọ́tà.

18 Ó máa dá ẹrù rẹ̀ pa dà láìlò ó;*

Kò ní gbádùn ọrọ̀ tó bá rí látinú òwò rẹ̀.+

19 Torí ó ti tẹ aláìní rẹ́, ó sì pa á tì;

Ó ti gba ilé tí kò kọ́.

20 Àmọ́ kò ní ní àlàáfíà rárá nínú ara rẹ̀;

Ọrọ̀ rẹ̀ kò ní gbà á sílẹ̀.

21 Ohunkóhun ò ní ṣẹ́ kù fún un láti jẹ;

Ìdí nìyẹn tí aásìkí rẹ̀ kò fi ní tọ́jọ́.

22 Tí ọrọ̀ rẹ̀ bá pọ̀ dé ẹ̀kúnrẹ́rẹ́, àníyàn máa gbà á lọ́kàn;

Gbogbo agbára ni àjálù máa fi kọ lù ú.

23 Bó ṣe ń fi nǹkan síkùn,

Ọlọ́run* máa bínú sí i gidigidi,

Ó máa rọ̀jò rẹ̀ lé e lórí wọnú ìfun rẹ̀.

24 Tó bá ń sá fún àwọn ohun ìjà irin,

Àwọn ọfà tí wọ́n fi ọrun bàbà ta máa gún un.

25 Ó fa ọfà kan yọ láti ẹ̀yìn rẹ̀,

Ohun ìjà tó ń dán yinrin látinú òróòro rẹ̀,

Jìnnìjìnnì sì bò ó.+

26 Òkùnkùn biribiri ń dúró de àwọn ìṣúra rẹ̀;

Iná tí ẹnì kankan ò fẹ́ atẹ́gùn sí máa jẹ ẹ́ run;

Àjálù máa bá ẹnikẹ́ni tó bá ṣẹ́ kù nínú àgọ́ rẹ̀.

27 Ọ̀run máa tú ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ síta;

Ayé máa dìde sí i.

28 Àkúnya omi máa gbé ilé rẹ̀ lọ;

Ọ̀gbàrá máa pọ̀ gan-an ní ọjọ́ ìbínú Ọlọ́run.*

29 Èyí ni ìpín ẹni burúkú látọ̀dọ̀ Ọlọ́run,

Ogún tí Ọlọ́run ti pín fún un.”

21 Jóòbù fèsì pé:

 2 “Ẹ fara balẹ̀ fetí sí ọ̀rọ̀ mi;

Kí èyí jẹ́ ohun tí ẹ fi máa tù mí nínú.

 3 Ẹ gba tèmi rò tí mo bá ń sọ̀rọ̀;

Tí mo bá sọ̀rọ̀ tán, ẹ lè wá fi mí ṣe yẹ̀yẹ́.+

 4 Ṣé èèyàn kan ni mò ń ṣàròyé fún ni?

Tó bá rí bẹ́ẹ̀, ṣé mo* máa lè ní sùúrù?

 5 Ẹ wò mí, kí ẹnu sì yà yín;

Ẹ fi ọwọ́ bo ẹnu yín.

 6 Tí mo bá ń rò ó, ọkàn mi kì í balẹ̀,

Gbogbo ara mi sì ń gbọ̀n rìrì.

 7 Kí ló dé tí àwọn ẹni burúkú ṣì fi wà láàyè,+

Tí wọ́n ń darúgbó, tí wọ́n sì ń di ọlọ́rọ̀?*+

 8 Gbogbo ìgbà ni àwọn ọmọ wọn ń wà lọ́dọ̀ wọn,

Wọ́n sì ń rí àtọmọdọ́mọ wọn.

 9 Ààbò wà lórí ilé wọn, wọn ò bẹ̀rù rárá,+

Ọlọ́run ò sì fi ọ̀pá rẹ̀ jẹ wọ́n níyà.

10 Akọ màlúù wọn ń gùn, kì í sì í tàsé;

Abo màlúù wọn ń bímọ, oyún ò sì bà jẹ́ lára wọn.

11 Àwọn ọmọkùnrin wọn ń sáré jáde bí agbo ẹran,

Àwọn ọmọ wọn sì ń ta pọ́n-ún pọ́n-ún.

12 Wọ́n ń lo ìlù tanboríìnì àti háàpù bí wọ́n ṣe ń kọrin,

Ìró fèrè* sì ń múnú wọn dùn.+

13 Ọkàn wọn balẹ̀ bí wọ́n ṣe ń lo ọjọ́ ayé wọn,

Wọ́n sì lọ sínú Isà Òkú* ní àlàáfíà.*

14 Àmọ́ wọ́n sọ fún Ọlọ́run tòótọ́ pé, ‘Fi wá sílẹ̀!

Kò wù wá pé ká mọ àwọn ọ̀nà rẹ.+

15 Ta ni Olódùmarè, tí a fi máa sìn ín?+

Èrè wo la máa rí tí a bá mọ̀ ọ́n?’+

16 Àmọ́ mo mọ̀ pé agbára wọn kọ́ ló mú wọn láásìkí.+

Èrò* àwọn ẹni burúkú jìnnà sí mi.+

17 Ìgbà mélòó là ń fẹ́ fìtílà àwọn ẹni burúkú pa?+

Ìgbà mélòó ni àjálù ń dé bá wọn?

Ìgbà mélòó ni Ọlọ́run ń fi ìbínú pa wọ́n run?

18 Ṣé wọ́n dà bíi pòròpórò rí níwájú atẹ́gùn

Àti bí ìyàngbò* tí ìjì gbé lọ?

19 Ọlọ́run máa fi ìyà èèyàn pa mọ́ de àwọn ọmọ rẹ̀;

Àmọ́ kí Ọlọ́run san án lẹ́san, kó bàa lè mọ̀ ọ́n.+

20 Kó fi ojú ara rẹ̀ rí ìparun rẹ̀,

Kí òun fúnra rẹ̀ sì mu nínú ìbínú Olódùmarè.+

21 Torí kí ló ṣe ń ronú ohun tó máa ṣẹlẹ̀ sí ilé rẹ̀ lẹ́yìn rẹ̀,

Tí a bá gé iye oṣù rẹ̀ kúrú?*+

22 Ṣé ẹnì kankan lè kọ́ Ọlọ́run ní ohunkóhun,*+

Nígbà tó jẹ́ pé Òun ló ń dá ẹjọ́ àwọn ẹni gíga jù pàápàá?+

23 Ẹnì kan kú nígbà tó ṣì lókun,+

Nígbà tí ara tù ú gan-an, tí ọkàn rẹ̀ sì balẹ̀,+

24 Nígbà tí ọ̀rá kún itan rẹ̀,

Tí egungun rẹ̀ sì le.*

25 Àmọ́ ẹlòmíì kú nínú ìbànújẹ́,*

Láì gbádùn ohun rere kankan rí.

26 Wọ́n jọ máa dùbúlẹ̀ sínú erùpẹ̀ ni,+

Ìdin sì máa bo àwọn méjèèjì.+

27 Ẹ wò ó! Mo mọ ohun tí ẹ̀ ń rò gangan

Àti àwọn ohun tí ẹ̀ ń gbèrò láti fi ṣe mí níkà.*+

28 Torí ẹ sọ pé, ‘Ibo ni ilé ẹni tó gbajúmọ̀ wà,

Ibo sì ni àgọ́ tí ẹni burúkú gbé wà?’+

29 Ṣebí ẹ ti béèrè ọ̀rọ̀ lọ́wọ́ àwọn arìnrìn-àjò?

Ṣebí ẹ̀ ń fara balẹ̀ wo àwọn ohun tí wọ́n rí,*

30 Pé à ń dá ẹni ibi sí ní ọjọ́ àjálù,

A sì ń gbà á sílẹ̀ ní ọjọ́ ìbínú?

31 Ta ló máa kò ó lójú nípa ọ̀nà rẹ̀,

Ta ló sì máa san án lẹ́san ohun tó ṣe?

32 Tí wọ́n bá gbé e lọ sí itẹ́ òkú,

Wọ́n máa ṣọ́ ibojì rẹ̀.

33 Iyẹ̀pẹ̀ tó ṣù pọ̀ ní àfonífojì máa dùn mọ́ ọn lẹ́nu,+

Gbogbo aráyé sì ń tẹ̀ lé e,*+

Bí àìmọye tó ṣáájú rẹ̀.

34 Kí ló dé tí ẹ wá ń fún mi ní ìtùnú tí kò nítumọ̀?+

Ẹ̀tàn ni gbogbo ìdáhùn yín!”

22 Élífásì+ ará Témánì fèsì pé:

 2 “Ṣé èèyàn wúlò fún Ọlọ́run?

Ṣé ẹni tó ní ìjìnlẹ̀ òye lè ṣe é láǹfààní?+

 3 Tí o bá jẹ́ olódodo, kí ló kan Olódùmarè,*

Àbí ó jèrè kankan torí pé o rìn ní ọ̀nà ìwà títọ́?+

 4 Ṣé ó máa fìyà jẹ ọ́,

Kó sì bá ọ ṣe ẹjọ́ torí pé o bẹ̀rù rẹ̀?

 5 Ṣé kì í ṣe torí pé ìwà burúkú rẹ pọ̀ jù ni,

Tí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ ò sì lópin?+

 6 Torí o gba ohun ìdúró lọ́wọ́ àwọn arákùnrin rẹ láìnídìí,

O sì bọ́ aṣọ lára àwọn èèyàn, o wá fi wọ́n sílẹ̀ ní ìhòòhò.*+

 7 O ò fún ẹni tó ti rẹ̀ lómi mu,

O ò sì fún ẹni tí ebi ń pa lóúnjẹ.+

 8 Alágbára ọkùnrin + ló ni ilẹ̀,

Ẹni tó rí ojúure sì ń gbé ibẹ̀.

 9 Àmọ́, o ní kí àwọn opó máa lọ lọ́wọ́ òfo,

O sì ṣẹ́ apá àwọn ọmọ aláìníbaba.*

10 Ìdí nìyẹn tí pańpẹ́*+ fi yí ọ ká,

Tí jìnnìjìnnì sì ṣàdédé bá ọ;

11 Ìdí nìyẹn tí òkùnkùn fi bò ọ́ débi pé o ò lè ríran,

Tí àkúnya omi sì bò ọ́ mọ́lẹ̀.

12 Ṣebí Ọlọ́run wà lókè nínú ọ̀run?

Tún wo bí gbogbo ìràwọ̀ ṣe ga tó.

13 Àmọ́, o sọ pé: ‘Kí ni Ọlọ́run tiẹ̀ mọ̀?

Ṣé ó lè ṣèdájọ́ látinú ìṣúdùdù tó kàmàmà?

14 Àwọsánmà* bò ó lójú, kò jẹ́ kó ríran,

Ó sì ń rìn kiri ní ìsálú* ọ̀run.’

15 Ṣé o máa gba ọ̀nà àtijọ́

Tí àwọn èèyàn burúkú rìn,

16 Àwọn èèyàn tí a yára mú lọ,* kí àkókò wọn tó pé,

Tí àkúnya omi* gbé ìpìlẹ̀ wọn lọ?+

17 Wọ́n ń sọ fún Ọlọ́run tòótọ́ pé: ‘Fi wá sílẹ̀!’

Àti pé, ‘Kí ni Olódùmarè lè ṣe fún wa?’

18 Síbẹ̀, òun ni Ó fi ohun rere kún àwọn ilé wọn.

(Irú èrò burúkú bẹ́ẹ̀ jìnnà sí tèmi.)

19 Olódodo máa rí èyí, á sì yọ̀,

Aláìmọwọ́-mẹsẹ̀ máa fi wọ́n ṣe yẹ̀yẹ́, á sì sọ pé:

20 ‘Àwọn ọ̀tá wa ti pa run,

Iná sì máa jó ohun tó bá ṣẹ́ kù lára wọn.’

21 Wá mọ̀ Ọ́n, wàá sì ní àlàáfíà;

Ohun rere á wá máa ṣẹlẹ̀ sí ọ.

22 Gba òfin láti ẹnu rẹ̀,

Kí o sì fi ọ̀rọ̀ rẹ̀ sínú ọkàn rẹ.+

23 Tí o bá pa dà sọ́dọ̀ Olódùmarè, wàá pa dà sí àyè rẹ;+

Tí o bá mú àìṣòdodo kúrò ní àgọ́ rẹ,

24 Tí o bá ju wúrà* rẹ sínú iyẹ̀pẹ̀,

Tí o sì ju wúrà Ófírì+ sínú àwọn àfonífojì àárín àpáta,

25 Olódùmarè á wá di wúrà* rẹ,

Ó sì máa di fàdákà rẹ tó dáa jù.

26 Ìgbà yẹn ni Olódùmarè máa múnú rẹ dùn,

Wàá sì yíjú sí Ọlọ́run lókè.

27 O máa bẹ̀ ẹ́, ó sì máa gbọ́ ọ;

Wàá sì san àwọn ẹ̀jẹ́ rẹ.

28 Ohunkóhun tí o bá pinnu pé o fẹ́ ṣe máa yọrí sí rere,

Ìmọ́lẹ̀ sì máa tàn sí ọ̀nà rẹ.

29 Torí ó máa rẹ̀ ọ́ wálẹ̀ tí o bá fi ìgbéraga sọ̀rọ̀,

Àmọ́ ó máa gba onírẹ̀lẹ̀* là.

30 Ó máa gba àwọn aláìṣẹ̀;

Torí náà, ó dájú pé tí ọwọ́ rẹ bá mọ́, ó máa gbà ọ́ sílẹ̀.”

23 Jóòbù fèsì pé:

 2 “Àní lónìí, màá fi orí kunkun ṣàròyé;*+

Okun mi ti tán torí ẹ̀dùn ọkàn mi.

 3 Ká ní mo mọ ibi tí mo ti lè rí Ọlọ́run ni!+

Ǹ bá lọ sí ibùgbé rẹ̀.+

 4 Màá ro ẹjọ́ mi níwájú rẹ̀,

Màá sì fi gbogbo ẹnu mi gbèjà ara mi;

 5 Màá fetí sí ìdáhùn tó bá fún mi,

Màá sì fọkàn sí ohun tó bá sọ fún mi.

 6 Ṣé ó máa fi agbára ńlá rẹ̀ bá mi jà?

Rárá, ó dájú pé ó máa gbọ́ mi.+

 7 Ibẹ̀ ni òun àti olóòótọ́ ti máa lè yanjú ọ̀rọ̀,

Adájọ́ mi sì máa dá mi láre títí láé.

 8 Àmọ́ tí mo bá lọ sí ìlà oòrùn, kò sí níbẹ̀;

Mo pa dà, mi ò sì rí i.

 9 Nígbà tó ń ṣiṣẹ́ lápá òsì, mi ò lè rí i;

Ó wá yí sí apá ọ̀tún, síbẹ̀ mi ò rí i.

10 Àmọ́, ó mọ ọ̀nà tí mo gbà.+

Lẹ́yìn tó bá dán mi wò, màá wá dà bíi wúrà tí wọ́n yọ́ mọ́.+

11 Ẹsẹ̀ mi tẹ̀ lé àwọn ìṣísẹ̀ rẹ̀ pẹ́kípẹ́kí;

Mò ń rìn ní ọ̀nà rẹ̀ ṣáá, mi ò sì yà kúrò níbẹ̀.+

12 Mi ò pa àṣẹ ẹnu rẹ̀ tì.

Mò ń pa àwọn ọ̀rọ̀ rẹ̀ mọ́+ ju ohun tó béèrè lọ́wọ́ mi* pàápàá.

13 Tó bá ti pinnu, ta ló lè dá a dúró?+

Tó* bá fẹ́ ṣe ohun kan, ó máa ṣe é.+

14 Torí ó máa ṣe gbogbo ohun tó ti pinnu* nípa mi,

Irú nǹkan wọ̀nyí sì pọ̀ lọ́dọ̀ rẹ̀.

15 Ìdí nìyẹn tí ọkàn mi ò fi balẹ̀ nítorí rẹ̀;

Tí mo bá ronú nípa rẹ̀, ẹ̀rù á túbọ̀ bà mí.

16 Ọlọ́run ti sọ mí di ojo,

Olódùmarè sì ti mú kí ẹ̀rù bà mí.

17 Àmọ́ òkùnkùn ò tíì pa mí lẹ́nu mọ́,

Ìṣúdùdù tó bò mí lójú kò sì tíì ṣe bẹ́ẹ̀.

24 “Kí ló dé tí Olódùmarè ò yan àkókò?+

Kí ló dé tí àwọn tó mọ̀ ọ́n kò rí ọjọ́ rẹ̀?*

 2 Àwọn èèyàn ń sún ààlà;+

Wọ́n ń jí àwọn agbo ẹran gbé lọ sí ibi ìjẹko wọn.

 3 Wọ́n ń lé kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ àwọn ọmọ aláìníbaba* dà nù,

Wọ́n sì ń gba akọ màlúù opó láti fi ṣe ìdúró.*+

 4 Wọ́n ń fipá lé àwọn aláìní kúrò lọ́nà;

Àfi kí àwọn tí kò ní olùrànlọ́wọ́ láyé sá pa mọ́ fún wọn.+

 5 Àwọn aláìní ń wá oúnjẹ kiri bíi kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ igbó+ nínú aginjù;

Wọ́n ń wá oúnjẹ kiri fún àwọn ọmọ wọn nínú aṣálẹ̀.

 6 Àfi kí wọ́n kórè nínú oko ẹlòmíì,*

Kí wọ́n sì pèéṣẹ́* nínú ọgbà àjàrà ẹni burúkú.

 7 Ìhòòhò ni wọ́n ń sùn mọ́jú, wọn ò ní aṣọ;+

Wọn ò rí nǹkan kan fi bora nígbà òtútù.

 8 Òjò orí òkè mú kí wọ́n rin gbingbin;

Wọ́n rọ̀ mọ́ àpáta torí wọn ò ríbi forí pa mọ́ sí.

 9 Wọ́n já ọmọ aláìníbaba gbà lẹ́nu ọmú;+

Wọ́n sì gba aṣọ aláìní láti fi ṣe ìdúró,+

10 Wọ́n fipá mú kí wọ́n máa rìn kiri ní ìhòòhò, láìwọ aṣọ,

Ebi sì ń pa wọ́n, bí wọ́n ṣe gbé àwọn ìtí ọkà.

11 Wọ́n ń ṣiṣẹ́ kára láàárín àwọn ògiri ilẹ̀ onípele nínú ooru ọ̀sán gangan;*

Wọ́n ń tẹ àjàrà níbi tí wọ́n ti ń fún wáìnì, síbẹ̀ òùngbẹ ń gbẹ wọ́n.+

12 Àwọn tó ń kú lọ ń kérora nínú ìlú;

Àwọn tó fara pa gan-an* ń kígbe fún ìrànlọ́wọ́,+

Àmọ́ Ọlọ́run ò ka èyí sí àìdáa.*

13 Àwọn kan wà tí wọ́n ṣọ̀tẹ̀ sí ìmọ́lẹ̀;+

Wọn ò mọ àwọn ọ̀nà rẹ̀,

Wọn kì í sì í tẹ̀ lé àwọn òpópónà rẹ̀.

14 Apààyàn dìde ní ojúmọmọ;

Ó pa ẹni tí kò ní olùrànlọ́wọ́ àti aláìní,+

Ó sì ń jalè ní òru.

15 Ojú alágbèrè ń dúró de ìrọ̀lẹ́,+

Ó ń sọ pé, ‘Kò sẹ́ni tó máa rí mi!’+

Ó sì ń bo ojú rẹ̀.

16 Wọ́n ń fọ́ ilé* nínú òkùnkùn;

Wọ́n ń ti ara wọn mọ́lé ní ọ̀sán.

Àjèjì ni wọ́n sí ìmọ́lẹ̀.+

17 Torí bákan náà ni àárọ̀ àti òkùnkùn biribiri rí fún wọn;

Wọ́n mọ àwọn ohun tó ń dẹ́rù bani nínú òkùnkùn biribiri.

18 Àmọ́ omi yára gbé wọn lọ.*

Ègún máa wà lórí ilẹ̀ wọn.+

Wọn ò ní pa dà sí àwọn ọgbà àjàrà wọn.

19 Bí ọ̀gbẹlẹ̀ àti ooru ṣe ń mú kí yìnyín yọ́ kó sì gbẹ,

Bẹ́ẹ̀ ni Isà Òkú* ń mú àwọn tó dẹ́ṣẹ̀ lọ!+

20 Ìyá rẹ̀* máa gbàgbé rẹ̀; ìdin máa fi ṣe oúnjẹ.

Wọn ò ní rántí rẹ̀ mọ́.+

A sì máa ṣẹ́ àìṣòdodo bí igi.

21 Ó ń rẹ́ àwọn àgàn jẹ,

Ó sì ń ni opó lára.

22 Ọlọ́run* máa fi okun rẹ̀ mú àwọn alágbára kúrò;

Bí wọ́n tiẹ̀ dìde, kò dájú pé wọ́n á ní ìyè.

23 Ọlọ́run* jẹ́ kí wọ́n dá ara wọn lójú, kí ọkàn wọn sì balẹ̀,+

Àmọ́ ojú rẹ̀ tó gbogbo ohun tí wọ́n ń ṣe.*+

24 A gbé wọn ga fúngbà díẹ̀, lẹ́yìn náà, wọn ò sí mọ́.+

A rẹ̀ wọ́n sílẹ̀,+ a sì kó wọn jọ bíi gbogbo èèyàn yòókù;

A gé wọn kúrò bí orí ọkà.

25 Ta ló wá lè mú mi ní onírọ́,

Tàbí kó sọ pé ọ̀rọ̀ mi kì í ṣòótọ́?”

25 Bílídádì+ ọmọ Ṣúáhì fèsì pé:

 2 “Tirẹ̀ ni àkóso àti agbára tó ń bani lẹ́rù;

Ó ń mú kí àlàáfíà jọba ní ọ̀run.*

 3 Ṣé àwọn ọmọ ogun rẹ̀ ṣeé kà?

Ta ni ìmọ́lẹ̀ rẹ̀ kì í tàn sí?

 4 Báwo wá ni ẹni kíkú ṣe lè jẹ́ olódodo níwájú Ọlọ́run,+

Àbí báwo ni ẹni tí obìnrin bí ṣe lè jẹ́ aláìṣẹ̀?*+

 5 Òṣùpá pàápàá kò mọ́lẹ̀,

Àwọn ìràwọ̀ ò sì mọ́ lójú rẹ̀,

 6 Ká má ṣẹ̀ṣẹ̀ wá sọ ti ẹni kíkú, tó jẹ́ ìdin

Àti ọmọ èèyàn, tó jẹ́ kòkòrò mùkúlú!”

26 Jóòbù wá fèsì pé:

 2 “Wo bí o ṣe ran ẹni tí kò lágbára lọ́wọ́!

Wo bí o ṣe gba apá tí kò lókun là!+

 3 Wo ìmọ̀ràn tó dáa gan-an tí o fún ẹni tí kò gbọ́n!+

Wo bí o ṣe fi ọgbọ́n rẹ tó gbéṣẹ́* hàn ní fàlàlà!*

 4 Ta lò ń gbìyànjú láti bá sọ̀rọ̀,

Ta ló sì mí sí ọ tí o fi ń sọ àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀?*

 5 Jìnnìjìnnì bá àwọn tí ikú ti pa;*

Wọ́n tiẹ̀ tún rẹlẹ̀ ju omi àtàwọn tó ń gbénú wọn.

 6 Ìhòòhò ni Isà Òkú* wà níwájú Ọlọ́run,*+

Ibi ìparun* sì wà láìfi ohunkóhun bò ó.

 7 Ó na òfúrufú apá àríwá* sórí ibi tó ṣófo,*+

Ó fi ayé rọ̀ sórí òfo;

 8 Ó wé omi mọ́ inú àwọsánmà* rẹ̀,+

Débi pé àwọsánmà ò bẹ́, bí wọ́n tiẹ̀ wúwo;

 9 Ó bo ìtẹ́ rẹ̀ ká má bàa rí i,

Ó na sánmà rẹ̀ bò ó.+

10 Ó pààlà* sójú òfúrufú àti omi;+

Ó fi ààlà sáàárín ìmọ́lẹ̀ àti òkùnkùn.

11 Àní àwọn òpó ọ̀run mì tìtì;

Ìbáwí rẹ̀ mú wọn wárìrì.

12 Ó fi agbára rẹ̀ ru òkun sókè,+

Ó sì fi òye rẹ̀ fọ́ ẹran ńlá inú òkun* sí wẹ́wẹ́.+

13 Ó fi èémí* rẹ̀ mú kí ojú ọ̀run mọ́ lóló;

Ọwọ́ rẹ̀ ń gún ejò tó ń yọ́ bọ́rọ́.*

14 Wò ó! Bíńtín lèyí jẹ́ lára àwọn ọ̀nà rẹ̀;+

Ọ̀rọ̀ kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́ lásán ló ta sí wa létí nípa rẹ̀!

Ta ló wá lè lóye ààrá ńlá rẹ̀?”+

27 Jóòbù ń bá ọ̀rọ̀* rẹ̀ lọ, ó ní:

 2 “Bó ṣe dájú pé Ọlọ́run wà láàyè, ẹni tó fi ìdájọ́ òdodo dù mí+

Àti bí Olódùmarè ti wà, ẹni tó mú kí n banú jẹ́,*+

 3 Tí èémí mi bá ṣì wà nínú mi,

Tí ẹ̀mí látọ̀dọ̀ Ọlọ́run sì wà nínú ihò imú mi,+

 4 Ètè mi ò ní sọ̀rọ̀ àìṣòdodo;

Ahọ́n mi ò sì ní sọ* ọ̀rọ̀ ẹ̀tàn!

 5 Kò ṣeé gbọ́ pé kí n pe ẹ̀yin ọkùnrin yìí ní olódodo!

Títí màá fi kú, mi ò ní fi ìwà títọ́ mi sílẹ̀!*+

 6 Màá rọ̀ mọ́ òdodo mi, mi ò sì ní jẹ́ kó lọ;+

Ọkàn mi ò ní dá mi lẹ́bi* tí mo bá ṣì wà láàyè.*

 7 Kó rí fún ọ̀tá mi bí ẹni burúkú,

Àwọn tó ń gbógun tì mí, bí aláìṣòdodo.

 8 Torí ìrètí wo ni ẹni tí kò mọ Ọlọ́run* ní tó bá pa run,+

Tí Ọlọ́run bá gba ẹ̀mí* rẹ̀?

 9 Ṣé Ọlọ́run máa gbọ́ igbe rẹ̀,

Tí wàhálà bá dé bá a?+

10 Àbí inú rẹ̀ á máa dùn nínú Olódùmarè?

Ṣé á máa ké pe Ọlọ́run nígbà gbogbo?

11 Màá kọ́ yín nípa agbára* Ọlọ́run;

Mi ò ní fi nǹkan kan pa mọ́ nípa Olódùmarè.

12 Ẹ wò ó! Tó bá jẹ́ pé gbogbo yín ti rí ìran,

Kí ló dé tí ọ̀rọ̀ yín kò nítumọ̀ rárá?

13 Èyí ni ìpín èèyàn burúkú látọ̀dọ̀ Ọlọ́run,+

Ogún tí àwọn oníwà ìkà gbà látọ̀dọ̀ Olódùmarè.

14 Tí àwọn ọmọ rẹ̀ bá pọ̀, wọ́n á fi idà pa wọ́n,+

Àwọn àtọmọdọ́mọ rẹ̀ ò sì ní ní oúnjẹ tó máa tó wọn.

15 Àjàkálẹ̀ àrùn ló máa sin àwọn tó bá gbẹ̀yìn rẹ̀,

Àwọn opó wọn ò sì ní sunkún nítorí wọn.

16 Tó bá tiẹ̀ to fàdákà jọ pelemọ bí erùpẹ̀,

Tó sì kó aṣọ olówó ńlá jọ bí amọ̀,

17 Bó tiẹ̀ kó o jọ,

Olódodo ló máa wọ̀ ọ́,+

Aláìṣẹ̀ sì máa pín fàdákà rẹ̀.

18 Ilé tó kọ́ kò lágbára, ó dà bí ilé òólá,*

Bí àtíbàbà+ tí ẹ̀ṣọ́ ṣe.

19 Ó máa lọ́rọ̀ nígbà tó bá dùbúlẹ̀, àmọ́ kò ní kó nǹkan kan jọ;

Nígbà tó bá la ojú rẹ̀, kò ní sí nǹkan kan níbẹ̀.

20 Ìbẹ̀rù bò ó bí àkúnya omi;

Ìjì gbé e lọ ní òru.+

21 Atẹ́gùn ìlà oòrùn máa gbé e lọ, kò sì ní sí mọ́;

Ó gbá a lọ kúrò ní àyè rẹ̀.+

22 Ó máa kọ lù ú, kò sì ní ṣàánú rẹ̀+

Bó ṣe ń gbìyànjú gbogbo ọ̀nà láti sá lọ kúrò lọ́wọ́ agbára rẹ̀.+

23 Ó pàtẹ́wọ́ sí i,

Ó sì súfèé+ sí i láti àyè rẹ̀.*

28 “Ibì kan wà tí wọ́n ti lè wa fàdákà,

Ibì kan sì wà tí wúrà tí wọ́n yọ́ mọ́ wà;+

 2 Inú ilẹ̀ ni wọ́n ti ń mú irin,

Inú àpáta sì ni wọ́n ti ń yọ́ bàbà.*+

 3 Èèyàn ń borí òkùnkùn;

Ó ń wá ibi gbogbo nínú ìṣúdùdù àti òkùnkùn,

Ó ń wá òkúta iyebíye.*

 4 Ó gbẹ́ ihò jìnnà sí ibi tí àwọn èèyàn ń gbé,

Láwọn ibi tí wọ́n ti gbàgbé, tó jìnnà síbi táwọn èèyàn ń gbà kọjá;

Àwọn èèyàn kan sọ̀ kalẹ̀, wọ́n sì rọ̀ dirodiro.

 5 Oúnjẹ ń hù lórí ilẹ̀;

Àmọ́ nísàlẹ̀, nǹkan ń dà rú, bí ìgbà tí iná ń jó.*

 6 Sàfáyà wà nínú òkúta níbẹ̀,

Wúrà sì wà nínú iyẹ̀pẹ̀.

 7 Kò sí ẹyẹ aṣọdẹ tó mọ ọ̀nà débẹ̀;

Ojú àwòdì dúdú kò rí i.

 8 Àwọn ẹranko ńlá ò tẹ̀ ẹ́ mọ́lẹ̀ rí;

Ọmọ kìnnìún ò rìn kiri níbẹ̀.

 9 Èèyàn fi ọwọ́ rẹ̀ lu akọ òkúta;

Ó dojú àwọn òkè dé níbi ìpìlẹ̀ wọn.

10 Ó la ọ̀nà sínú àpáta fún omi;+

Ojú rẹ̀ ń rí gbogbo ohun tó ṣeyebíye.

11 Ó ń sé àwọn orísun odò,

Ó sì ń mú àwọn ohun tó pa mọ́ wá sínú ìmọ́lẹ̀.

12 Àmọ́ ibo la ti lè rí ọgbọ́n,+

Ibo sì ni orísun òye?+

13 Kò sí èèyàn tó mọ bó ṣe níye lórí tó,+

A ò sì lè rí i ní ilẹ̀ alààyè.

14 Ibú omi sọ pé, ‘Kò sí nínú mi!’

Òkun sì sọ pé, ‘Kò sí lọ́dọ̀ mi!’+

15 Kò ṣeé fi ògidì wúrà rà;

A kò sì lè díwọ̀n fàdákà láti fi pààrọ̀ rẹ̀.+

16 Kò ṣeé fi wúrà Ófírì rà,+

Kò sì ṣeé fi òkúta ónísì tó ṣọ̀wọ́n àti sàfáyà rà.

17 Wúrà àti gíláàsì kò ṣeé fi wé e;

A kò lè fi ohun èlò èyíkéyìí tí wọ́n fi wúrà tó dáa* ṣe pààrọ̀ rẹ̀.+

18 A ò lè mẹ́nu kan iyùn àti òkúta kírísítálì,+

Torí ẹ̀kún àpò ọgbọ́n níye lórí ju àpò tí péálì kún inú rẹ̀.

19 Tópásì + ti Kúṣì kò ṣeé fi wé e;

Ògidì wúrà pàápàá kò lè rà á.

20 Àmọ́ ibo ni ọgbọ́n ti wá,

Ibo sì ni orísun òye?+

21 Ó ti fara sin kúrò lójú gbogbo ohun alààyè,+

Ó sì pa mọ́ fún àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run.

22 Ìparun àti ikú sọ pé,

‘Ìròyìn rẹ̀ nìkan ló dé etí wa.’

23 Ọlọ́run mọ bí a ṣe lè rí i;

Òun nìkan ló mọ ibi tó ń gbé,+

24 Torí ó ń wo ayé títí dé àwọn ìkángun rẹ̀,

Ó sì ń rí gbogbo ohun tó wà lábẹ́ ọ̀run.+

25 Nígbà tó fún afẹ́fẹ́ ní agbára,*+

Tó sì díwọ̀n omi,+

26 Nígbà tó gbé ìlànà kalẹ̀ fún òjò,+

Tó sì lànà fún ìjì tó ń sán ààrá nínú ìkùukùu,*+

27 Ó wá rí ọgbọ́n, ó sì ṣàlàyé rẹ̀;

Ó fìdí rẹ̀ múlẹ̀, ó sì dán an wò.

28 Ó sì sọ fún èèyàn pé:

‘Wò ó! Ìbẹ̀rù Jèhófà ni ọgbọ́n,+

Yíyẹra fún ìwà burúkú sì ni òye.’”+

29 Jóòbù ń bá ọ̀rọ̀* rẹ̀ lọ, ó ní:

 2 “Ká sọ pé àwọn oṣù tó ti kọjá ni mo wà,

Láwọn ọjọ́ tí Ọlọ́run ń ṣọ́ mi,

 3 Nígbà tó mú kí fìtílà rẹ̀ tàn sí mi lórí,

Nígbà tí mo fi ìmọ́lẹ̀ rẹ̀ rìn nínú òkùnkùn,+

 4 Nígbà tí mo ṣì lókun,*

Nígbà tí mo mọ bó ṣe ń rí kéèyàn jẹ́ ọ̀rẹ́ Ọlọ́run nínú àgọ́ mi,+

 5 Nígbà tí Olódùmarè ṣì wà pẹ̀lú mi,

Nígbà tí àwọn ọmọ* mi yí mi ká,

 6 Nígbà tí bọ́tà bo àwọn ìṣísẹ̀ mi,

Tí àwọn àpáta sì ń tú ìṣàn òróró jáde fún mi.+

 7 Nígbà tí mo ṣì máa ń jáde lọ sí ẹnubodè ìlú,+

Tí mo sì máa ń jókòó sí ojúde ìlú,+

 8 Àwọn ọ̀dọ́kùnrin máa rí mi, wọ́n á sì yà sẹ́gbẹ̀ẹ́,*

Àwọn àgbà ọkùnrin pàápàá máa dìde, wọ́n á sì wà ní ìdúró.+

 9 Àwọn ìjòyè máa ń dákẹ́;

Wọ́n á fi ọwọ́ bo ẹnu wọn.

10 Àwọn gbajúmọ̀ ọkùnrin panu mọ́;

Ahọ́n wọn lẹ̀ mọ́ òkè ẹnu wọn.

11 Ẹnikẹ́ni tó bá gbọ́ mi máa ń sọ̀rọ̀ mi dáadáa,

Àwọn tó sì rí mi máa ń ṣe ẹlẹ́rìí mi.

12 Torí mo máa ń gba aláìní tó ń kígbe fún ìrànlọ́wọ́ sílẹ̀,+

Pẹ̀lú ọmọ aláìníbaba* àti ẹnikẹ́ni tí kò ní olùrànlọ́wọ́.+

13 Ẹni tó ń kú lọ máa ń súre fún mi,+

Mo sì ń mú kí inú opó dùn.+

14 Mo wọ òdodo bí aṣọ;

Ìdájọ́ òdodo mi dà bí ẹ̀wù* àti láwàní.

15 Mo di ojú fún afọ́jú

Àti ẹsẹ̀ fún arọ.

16 Mo jẹ́ bàbá fún àwọn aláìní;+

Mo máa ń wádìí ẹjọ́ àwọn tí mi ò mọ̀.+

17 Mo máa ń fọ́ páárì ẹ̀rẹ̀kẹ́ ẹni burúkú,+

Mo sì máa ń já ẹran gbà kúrò ní eyín rẹ̀.

18 Mo máa ń sọ pé, ‘Inú ilé mi* ni màá kú sí,+

Ọjọ́ ayé mi á sì pọ̀ bí iyanrìn.

19 Màá ta gbòǹgbò wọnú omi,

Ìrì á sì wà lórí àwọn ẹ̀ka mi mọ́jú.

20 Ògo mi ń di ọ̀tun ní gbogbo ìgbà,

Màá sì máa ta ọfà ọwọ́ mi léraléra.’

21 Àwọn èèyàn máa ń fẹ́ gbọ́ mi,

Wọ́n á dákẹ́, wọ́n á máa retí ìmọ̀ràn mi.+

22 Tí mo bá ti sọ̀rọ̀, wọn kì í tún ní ohunkóhun láti sọ;

Ọ̀rọ̀ mi máa ń rọra wọ̀ wọ́n* létí.

23 Wọ́n ń dúró dè mí bí ẹni ń dúró de òjò;

Wọ́n la ẹnu wọn sílẹ̀ gbayawu bíi fún òjò ìrúwé.+

24 Nígbà tí mo rẹ́rìn-ín músẹ́ sí wọn, ó yà wọ́n lẹ́nu gan-an;

Ìmọ́lẹ̀ ojú mi máa ń fi wọ́n lọ́kàn balẹ̀.*

25 Mò ń darí wọn gẹ́gẹ́ bí olórí wọn,

Mo sì ń gbé bí ọba láàárín àwọn ọmọ ogun rẹ̀,+

Bí ẹni tó ń tu àwọn tó ń ṣọ̀fọ̀ nínú.+

30 “Wọ́n ti ń fi mí rẹ́rìn-ín báyìí,+

Àwọn ọkùnrin tí kò tó mi lọ́jọ́ orí,

Àwọn tí mi ò lè gbà kí bàbá wọn

Dúró lẹ́gbẹ̀ẹ́ àwọn ajá tó ń ṣọ́ agbo ẹran mi.

 2 Àǹfààní wo ni agbára ọwọ́ wọn ṣe mí?

Okun wọn ti ṣègbé.

 3 Àìní àti ebi ti tán wọn lókun;

Wọ́n ń họ ilẹ̀ gbígbẹ jẹ,

Ilẹ̀ tó ti pa run, tó sì ti di ahoro.

 4 Wọ́n ń kó ewé iyọ̀ jọ látinú igbó;

Gbòǹgbò igi wíwẹ́ ni oúnjẹ wọn.

 5 Wọ́n lé wọn kúrò ní ìlú;+

Àwọn èèyàn kígbe mọ́ wọn bí ẹni ń kígbe mọ́ olè.

 6 Wọ́n ń gbé ní gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ àfonífojì tó jin kòtò,

Nínú àwọn ihò inú ilẹ̀ àti inú àpáta.

 7 Wọ́n ń ké jáde látinú igbó,

Wọ́n sì kó ara wọn jọ sí àárín èsìsì.

 8 A ti lé wọn kúrò* ní ilẹ̀ náà,

Bí àwọn ọmọ òpònú àti àwọn tí kò lórúkọ.

 9 Àmọ́ wọ́n ń fi mí ṣe yẹ̀yẹ́ báyìí kódà nínú orin wọn;+

Mo ti di ẹni ẹ̀gàn* lójú wọn.+

10 Wọ́n kórìíra mi, wọ́n sì jìnnà sí mi;+

Ó yá wọn lára láti tutọ́ sí mi lójú.+

11 Torí Ọlọ́run ti gba ohun ìjà mi,* ó sì rẹ̀ mí sílẹ̀,

Wọn ò kóra wọn níjàánu rárá* níwájú mi.

12 Wọ́n dìde ní ọwọ́ ọ̀tún mi bí àwọn jàǹdùkú;

Wọ́n mú kí n sá lọ,

Wọ́n sì fi àwọn ohun ìdènà tó ń fa ìparun sí ojú ọ̀nà mi.

13 Wọ́n ya àwọn ọ̀nà mi lulẹ̀,

Wọ́n sì mú kí àjálù tó dé bá mi le sí i,+

Láìsí ẹnikẹ́ni tó dá wọn dúró.*

14 Wọ́n wá bí ẹni pé ihò tó fẹ̀ lára ògiri ni wọ́n gbà kọjá;

Wọ́n ya wọlé nígbà ìṣòro.

15 Ìbẹ̀rù bò mí;

Wọ́n lé iyì mi lọ bí atẹ́gùn,

Ìgbàlà mi sì pòórá bí ìkùukùu.

16 Ní báyìí, ẹ̀mí* mi ń lọ kúrò nínú mi;+

Àwọn ọjọ́ ìpọ́njú+ gbá mi mú.

17 Egungun ń ro mí gan-an* ní òru,+

Ìrora tó ń já mi jẹ ò dáwọ́ dúró.+

18 A fi agbára ńlá sọ ẹ̀wù mi di ìdàkudà;*

Ó ń fún mọ́ mi lọ́rùn bí ọrùn aṣọ mi.

19 Ọlọ́run ti jù mí sínú ẹrọ̀fọ̀;

Ó ti mú kí n dà bí iyẹ̀pẹ̀ àti eérú.

20 Mo ké pè ọ́ pé kí o ràn mí lọ́wọ́, àmọ́ o ò dá mi lóhùn;+

Mo dìde dúró, àmọ́ ńṣe lo kàn ń wò mí.

21 O ṣe mí níkà, o sì kẹ̀yìn sí mi;+

O fi gbogbo agbára ọwọ́ rẹ gbéjà kò mí.

22 O gbé mi sókè, o sì fi atẹ́gùn gbé mi lọ;

O wá ń fi ìjì jù mí kiri.*

23 Torí mo mọ̀ pé wàá mú kí n kú,

Kí n lọ sí ibi tí gbogbo alààyè á ti pàdé.

24 Àmọ́ kò sẹ́ni tó máa lu ẹni tí ìbànújẹ́ bá,*+

Bó ṣe ń kígbe fún ìrànlọ́wọ́ nígbà tí àjálù bá a.

25 Ṣé mi ò sunkún torí àwọn tí ìṣòro dé bá?*

Ṣebí mo* banú jẹ́ torí aláìní?+

26 Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ire ni mò ń retí, ibi ló ṣẹlẹ̀;

Mo retí ìmọ́lẹ̀, àmọ́ òkùnkùn ló dé.

27 Inú mi tó ń dà rú kò dáwọ́ dúró;

Ọjọ́ ìpọ́njú dé bá mi.

28 Mò ń rìn káàkiri nínú ìbànújẹ́;+ kò sí ìmọ́lẹ̀.

Mo dìde nínú àpéjọ, mo sì kígbe fún ìrànlọ́wọ́.

29 Mo ti di arákùnrin àwọn ajáko*

Àti ọ̀rẹ́ àwọn abo ọmọ ògòǹgò.+

30 Awọ ara mi ti dúdú, ó sì ti re dà nù;+

Ooru* ti mú kí egungun mi gbóná.

31 Ọ̀fọ̀ nìkan ni háàpù mi wúlò fún,

Igbe ẹkún sì ni fèrè* mi wà fún.

31 “Mo ti bá ojú mi dá májẹ̀mú.+

Ṣé ó wá yẹ kí n máa tẹjú mọ́ wúńdíá?+

 2 Kí ló wá máa jẹ́ ìpín mi látọ̀dọ̀ Ọlọ́run lókè,

Ogún wo ni màá gbà látọ̀dọ̀ Olódùmarè lókè?

 3 Ṣebí jàǹbá ń dúró de ẹni burúkú,

Àjálù sì ń dúró de àwọn aṣebi?+

 4 Ṣebí ó ń rí àwọn ọ̀nà mi,+

Tó sì ń ka gbogbo ìṣísẹ̀ mi?

 5 Ṣé mo ti rìn nínú àìṣòótọ́* rí?

Ṣé ẹsẹ̀ mi ti yára ṣe ẹ̀tàn ni?+

 6 Kí Ọlọ́run wọ̀n mí lórí òṣùwọ̀n tó péye;+

Ó máa wá mọ ìwà títọ́ mi.+

 7 Tí ẹsẹ̀ mi bá yà kúrò lọ́nà,+

Tàbí tí ọkàn mi bá tẹ̀ lé ojú mi,+

Tàbí tí ọwọ́ mi di aláìmọ́,

 8 Kí n fún irúgbìn, kí ẹlòmíì sì jẹ ẹ́,+

Kí wọ́n sì fa ohun tí mo gbìn* tu.

 9 Tí ọkàn mi bá ti fà sí obìnrin kan,+

Tí mo sì lúgọ+ sẹ́nu ọ̀nà ọmọnìkejì mi,

10 Kí ìyàwó mi lọ ọkà fún ọkùnrin míì,

Kí àwọn ọkùnrin míì sì bá a lò pọ̀.*+

11 Torí ìwà àìnítìjú nìyẹn,

Ẹ̀ṣẹ̀ tí àwọn adájọ́+ gbọ́dọ̀ torí ẹ̀ jẹni níyà.

12 Ó máa jẹ́ iná tó ń jẹ nǹkan run tó sì ń run nǹkan,*+

Tó ń run gbòǹgbò èso mi látòkè délẹ̀ pàápàá.*

13 Tí mi ò bá ka ẹ̀tọ́ àwọn ìránṣẹ́kùnrin tàbí ìránṣẹ́bìnrin mi sí,

Nígbà tí wọ́n fẹ̀sùn kàn mí,*

14 Kí ni mo lè ṣe tí Ọlọ́run bá kò mí lójú?

Kí ni mo lè sọ tó bá béèrè ọ̀rọ̀ lọ́wọ́ mi?+

15 Ṣebí Ẹni tó dá mi nínú ilé ọlẹ̀ ló dá àwọn náà?+

Ǹjẹ́ kì í ṣe Ẹnì kan náà ló mọ wá kí wọ́n tó bí wa?*+

16 Tí mo bá kọ̀ láti fún àwọn aláìní ní ohun tí wọ́n fẹ́,+

Tàbí tí mo mú kí opó ba ojú jẹ́;*+

17 Tí mo bá dá jẹ oúnjẹ mi,

Tí mi ò fún àwọn ọmọ aláìlóbìí+ nínú rẹ̀;

18 (Torí láti ìgbà ọ̀dọ́ mi ni ọmọ aláìlóbìí* ti wà lọ́dọ̀ mi bí ẹni pé èmi ni bàbá rẹ̀,

Mo sì ń tọ́jú opó* láti kékeré.*)

19 Tí mo bá rí ẹnikẹ́ni tó ń ṣègbé torí kò ní aṣọ,

Tàbí aláìní tí kò ní ohun tó máa fi bora;+

20 Tí kò* bá súre fún mi,+

Bó ṣe ń fi irun àgùntàn mi mú kí ara rẹ̀ móoru;

21 Tí mo bá fi ẹ̀ṣẹ́ mi halẹ̀ mọ́ ọmọ aláìlóbìí,+

Nígbà tó nílò ìrànlọ́wọ́ mi ní ẹnubodè ìlú;*+

22 Kí apá* mi yẹ̀ kúrò ní èjìká mi,

Kí apá mi sì kán ní ìgúnpá.*

23 Torí ẹ̀rù àjálù látọ̀dọ̀ Ọlọ́run bà mí,

Mi ò sì lè dúró níwájú iyì rẹ̀.

24 Tí mo bá gbẹ́kẹ̀ lé wúrà,

Àbí tí mo sọ fún wúrà tó dáa pé, ‘Ìwọ ni ààbò mi!’+

25 Tó bá jẹ́ ọrọ̀ rẹpẹtẹ+ tí mo ní ló ń fún mi láyọ̀,

Torí mo ti kó ọ̀pọ̀ ohun ìní jọ;+

26 Tí mo bá rí i tí oòrùn ń ràn,*

Tàbí tí òṣùpá ń lọ nínú iyì rẹ̀;+

27 Tí ọkàn mi wá ń dọ́gbọ́n fà sí wọn,

Tí mo sì fẹnu ko ọwọ́ mi láti jọ́sìn wọn;+

28 Ẹ̀ṣẹ̀ tí àwọn adájọ́ gbọ́dọ̀ torí ẹ̀ jẹni níyà ni,

Torí màá ti fìyẹn sẹ́ Ọlọ́run tòótọ́ lókè.

29 Ṣé inú mi ti dùn rí torí pé ọ̀tá mi pa run,+

Tàbí kí n fi ṣe yẹ̀yẹ́ torí ohun burúkú ṣẹlẹ̀ sí i?

30 Mi ò jẹ́ kí ẹnu mi mú kí n dẹ́ṣẹ̀ rí,

Pé kí n búra pé kí ẹ̀mí* rẹ̀ bọ́.+

31 Ṣebí àwọn èèyàn tó wà ní àgọ́ mi ti sọ pé,

‘Ǹjẹ́ a lè rí ẹnikẹ́ni tí kò tíì jẹ oúnjẹ* rẹ̀ ní àjẹtẹ́rùn?’+

32 Kò sí àlejò* tó sun ìta mọ́jú;+

Mo ṣí ilẹ̀kùn mi sílẹ̀ fún arìnrìn-àjò.

33 Ṣé mo ti gbìyànjú láti bo ẹ̀ṣẹ̀ mi mọ́lẹ̀ rí bíi ti àwọn èèyàn yòókù,+

Pé kí n fi àṣìṣe mi pa mọ́ sínú àpò aṣọ mi?

34 Ṣé mo bẹ̀rù ohun tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn máa ṣe,

Àbí jìnnìjìnnì bá mi nítorí bí àwọn ìdílé yòókù ṣe ń pẹ̀gàn mi,

Tí mo wá dákẹ́, tí ẹ̀rù sì bà mí láti jáde?

35 Ká ní ẹnì kan lè fetí sí mi ni!+

Ǹ bá buwọ́ lùwé sí ohun tí mo sọ.*

Kí Olódùmarè dá mi lóhùn!+

Ká ní ẹni tó fẹ̀sùn kàn mí ti kọ ẹ̀sùn náà sínú ìwé ni!

36 Màá gbé e lé èjìká mi,

Màá sì dè é mọ́ orí mi bí adé.

37 Màá sọ gbogbo ìgbésẹ̀ tí mo gbé fún un;

Màá fìgboyà lọ bá a, bí ìjòyè ti ń ṣe.

38 Tí ilẹ̀ mi bá ké jáde sí mi,

Tí àwọn poro rẹ̀ sì jọ ń sunkún;

39 Tí mo bá ti jẹ èso rẹ̀ láìsan owó,+

Tàbí tí mo mú kí àwọn* tó ni ín máa dààmú;+

40 Kí ẹ̀gún hù jáde fún mi dípò àlìkámà*

Àti èpò tó ń rùn dípò ọkà bálì.”

Ibí ni ọ̀rọ̀ Jóòbù parí sí.

32 Àwọn ọkùnrin mẹ́ta yìí kò fún Jóòbù lésì mọ́, torí ó dá a lójú pé òun jẹ́ olódodo.*+ 2 Àmọ́ inú ti bí Élíhù ọmọ Bárákélì ọmọ Búsì+ láti ìdílé Rámù gan-an. Inú bí i gidigidi sí Jóòbù torí bó ṣe ń gbìyànjú láti fi hàn pé òun* jẹ́ olódodo ju Ọlọ́run lọ.+ 3 Inú tún bí i gidigidi sí àwọn ọ̀rẹ́ Jóòbù mẹ́tẹ̀ẹ̀ta torí wọn ò mọ bó ṣe yẹ kí wọ́n fèsì, àmọ́ wọ́n pe Ọlọ́run ní ẹni burúkú.+ 4 Élíhù ti ń dúró kó lè dá Jóòbù lóhùn, torí pé wọ́n dàgbà jù ú lọ.+ 5 Nígbà tí Élíhù rí i pé àwọn ọkùnrin mẹ́tẹ̀ẹ̀ta ò rí nǹkan kan sọ, inú bí i gidigidi. 6 Élíhù ọmọ Bárákélì ọmọ Búsì wá bẹ̀rẹ̀ sí í sọ̀rọ̀, ó ní:

“Ọmọdé ni mí,*

Àgbàlagbà sì ni ẹ̀yin.+

Ìdí nìyẹn tí mi ò fi sọ̀rọ̀ torí mo bọ̀wọ̀ fún yín,+

Mi ò sì jẹ́ sọ ohun tí mo mọ̀ fún yín.

 7 Mo ronú pé, ‘Kí ọjọ́ orí* sọ̀rọ̀,

Kí ọ̀pọ̀ ọdún sì kéde ìmọ̀.’

 8 Àmọ́ ẹ̀mí tó wà nínú àwọn èèyàn,

Èémí Olódùmarè, ló ń fún wọn ní òye.+

 9 Ọjọ́ orí nìkan kọ́ ló ń* sọ èèyàn di ọlọ́gbọ́n,

Bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe àwọn àgbà nìkan ló mọ ohun tó tọ́.+

10 Torí náà, mo sọ pé, ‘Ẹ fetí sí mi,

Màá sì sọ ohun tí mo mọ̀ fún yín.’

11 Ẹ wò ó! Mo ti dúró de ọ̀rọ̀ yín;

Mò ń fetí sí ìfèròwérò yín,+

Bí ẹ ṣe ń wá ohun tí ẹ máa sọ.+

12 Mo fara balẹ̀ tẹ́tí sí yín,

Àmọ́ ìkankan nínú yín ò lè fi hàn pé Jóòbù ṣàṣìṣe,*

Ẹ ò sì lè fún un lésì ọ̀rọ̀ rẹ̀.

13 Torí náà, ẹ má sọ pé, ‘A ti rí ọgbọ́n;

Ọlọ́run ló lè fi àṣìṣe rẹ̀ hàn, kì í ṣe èèyàn.’

14 Èmi kọ́ ló ń bá wí,

Torí náà, mi ò ní fi ọ̀rọ̀ yín fún un lésì.

15 Ìdààmú bá wọn, wọn ò lè fèsì mọ́;

Wọn ò ní ohunkóhun sọ mọ́.

16 Mo ti dúró, àmọ́ wọn ò sọ̀rọ̀ mọ́;

Wọ́n kàn dúró síbẹ̀, wọn ò fèsì mọ́.

17 Torí náà, èmi náà máa dáhùn;

Èmi náà máa sọ ohun tí mo mọ̀;

18 Torí nǹkan pọ̀ tí mo fẹ́ sọ;

Ẹ̀mí tó wà nínú mi ń fipá mú mi.

19 Inú mi dà bíi wáìnì tí wọ́n dé pa,

Bí àwọn ìgò awọ tuntun tó ti fẹ́ bẹ́.+

20 Jẹ́ kí n sọ̀rọ̀, kí ara lè tù mí!

Màá la ẹnu mi, màá sì fèsì.

21 Mi ò ní ṣe ojúsàájú sí ẹnikẹ́ni;+

Mi ò sì ní fi ọ̀rọ̀ dídùn pọ́n ẹnikẹ́ni,*

22 Torí mi ò mọ bí wọ́n ṣe ń fi ọ̀rọ̀ dídùn pọ́n èèyàn;

Tí mo bá ṣe bẹ́ẹ̀, Ẹni tó dá mi máa yára mú mi kúrò.

33 “Àmọ́ ní báyìí, Jóòbù, jọ̀ọ́ gbọ́ ọ̀rọ̀ mi;

Fetí sí gbogbo ohun tí mo fẹ́ sọ.

 2 Jọ̀ọ́, wò ó! Mo gbọ́dọ̀ la ẹnu mi;

Ahọ́n mi* gbọ́dọ̀ sọ̀rọ̀.

 3 Àwọn ọ̀rọ̀ mi fi òótọ́ ọkàn+ mi hàn,

Ètè mi sì ń fi òótọ́ inú sọ ohun tí mo mọ̀.

 4 Ẹ̀mí Ọlọ́run ló ṣẹ̀dá mi,+

Èémí Olódùmarè fúnra rẹ̀ ló sì fún mi ní ìyè.+

 5 Dá mi lóhùn tí o bá lè ṣe bẹ́ẹ̀;

Gbèjà ara rẹ níwájú mi; mú ìdúró rẹ.

 6 Wò ó! Bákan náà ni èmi àti ìwọ rí níwájú Ọlọ́run tòótọ́;

Amọ̀ ni ó fi mọ+ èmi náà.

 7 Torí náà, má ṣe jẹ́ kí ẹ̀rù mi bà ọ́ rárá,

Má sì jẹ́ kí jìnnìjìnnì bò ọ́ mọ́lẹ̀ nítorí mi.

 8 Àmọ́, o sọ ọ́ létí mi,

Àní mo ṣáà ń gbọ́ tí ò ń sọ pé,

 9 ‘Mo mọ́, mi ò ní ẹ̀ṣẹ̀ lọ́rùn;+

Mo mọ́, mi ò ní àṣìṣe.+

10 Àmọ́ Ọlọ́run rí ìdí tó fi yẹ kó ta kò mí;

Ó kà mí sí ọ̀tá rẹ̀.+

11 Ó ti ẹsẹ̀ mi mọ́ inú àbà;

Ó ń ṣọ́ gbogbo ọ̀nà mi lójú méjèèjì.’+

12 Àmọ́ ohun tí o sọ yìí ò tọ́, torí náà, màá dá ọ lóhùn:

Ọlọ́run tóbi ju ẹni kíkú+ lọ fíìfíì.

13 Kí nìdí tí o fi ń ṣàròyé nípa Rẹ̀?+

Ṣé torí pé kò fèsì gbogbo ọ̀rọ̀ tí o sọ ni?+

14 Torí Ọlọ́run ń sọ̀rọ̀ lẹ́ẹ̀kan àti lẹ́ẹ̀kejì,

Àmọ́ kò sẹ́ni tó ń fiyè sí i,

15 Lójú àlá, nínú ìran òru,+

Nígbà tí àwọn èèyàn ti sùn lọ fọnfọn,

Bí wọ́n ṣe ń sùn lórí ibùsùn wọn.

16 Lẹ́yìn náà, ó máa ṣí etí wọn,+

Ó sì máa tẹ* ìtọ́ni rẹ̀ mọ́ wọn lọ́kàn,

17 Láti yí èèyàn kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀,+

Kó sì gba èèyàn lọ́wọ́ ìgbéraga.+

18 Ọlọ́run ò jẹ́ kí ọkàn* rẹ̀ wọnú kòtò,*+

Kò jẹ́ kí idà* gba ẹ̀mí rẹ̀.

19 Ìrora téèyàn ń ní lórí ibùsùn rẹ̀ máa ń bá a wí,

Bẹ́ẹ̀ sì ni ìnira tó ń bá egungun rẹ̀ léraléra,

20 Tí òun fúnra rẹ̀* fi kórìíra búrẹ́dì gidigidi,

Tó* sì kọ oúnjẹ tó dáa + pàápàá.

21 Ẹran ara rẹ̀ ń joro lọ lójú,

Egungun rẹ̀ tí a kò rí tẹ́lẹ̀ ti wá yọ síta.*

22 Ọkàn* rẹ̀ ti sún mọ́ kòtò;*

Ẹ̀mí rẹ̀ sì ti sún mọ́ àwọn tó ń pani.

23 Tí ìránṣẹ́* kan bá wá jíṣẹ́ fún un,

Agbẹnusọ kan nínú ẹgbẹ̀rún (1,000),

Láti sọ ohun tó tọ́ fún èèyàn,

24 Ọlọ́run máa wá ṣe ojúure sí i, á sì sọ pé,

‘Dá ẹ̀mí rẹ̀ sí, kó má bàa lọ sínú kòtò!*+

Mo ti rí ìràpadà!+

25 Kí ara rẹ̀ jọ̀lọ̀* ju ti ìgbà ọ̀dọ́;+

Kó pa dà sí àwọn ọjọ́ tó lókun nígbà ọ̀dọ́.’+

26 Ó máa bẹ Ọlọ́run,+ ẹni tó máa gbà á,

Ó máa rí ojú Rẹ̀ tòun ti igbe ayọ̀,

Ó sì máa dá òdodo Rẹ̀ pa dà fún ẹni kíkú.

27 Ẹni yẹn máa kéde* fún àwọn èèyàn pé,

‘Mo ti ṣẹ̀,+ mo sì ti yí ohun tó tọ́ po,

Àmọ́ mi ò rí ohun tó tọ́ sí mi gbà.*

28 Ó ti ra ọkàn* mi pa dà kó má bàa lọ sínú kòtò,*+

Ẹ̀mí mi sì máa rí ìmọ́lẹ̀.’

29 Lóòótọ́, Ọlọ́run máa ń ṣe gbogbo nǹkan yìí

Fún èèyàn, lẹ́ẹ̀mejì, lẹ́ẹ̀mẹta,

30 Láti mú un* pa dà kúrò nínú kòtò,*

Kí ìmọ́lẹ̀ ìyè+ lè là á lóye.

31 Fiyè sílẹ̀, Jóòbù! Fetí sí mi!

Dákẹ́, kí n sì máa sọ̀rọ̀ lọ.

32 Tí o bá ní nǹkan sọ, fún mi lésì.

Sọ̀rọ̀, torí mo fẹ́ fi hàn pé o jàre.

33 Tí kò bá sí ohun tí o fẹ́ sọ, kí o fetí sí mi;

Dákẹ́, màá sì kọ́ ọ ní ọgbọ́n.”

34 Élíhù ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ pé:

 2 “Ẹ fetí sí ọ̀rọ̀ mi, ẹ̀yin ọlọ́gbọ́n;

Ẹ gbọ́ mi, ẹ̀yin tí ẹ mọ nǹkan púpọ̀.

 3 Torí etí máa ń dán ọ̀rọ̀ wò,

Bí ahọ́n* ṣe ń tọ́ oúnjẹ wò.

 4 Ẹ jẹ́ ká fúnra wa ṣàyẹ̀wò ohun tó tọ́;

Ẹ jẹ́ ká pinnu ohun tó dáa láàárín ara wa.

 5 Torí Jóòbù sọ pé, ‘Mo jàre,+

Àmọ́ Ọlọ́run ti fi ìdájọ́ òdodo dù mí.+

 6 Ṣé màá parọ́ nípa ẹjọ́ tó yẹ kí wọ́n dá fún mi ni?

Ọgbẹ́ mi ò ṣeé wò sàn, bí mi ò tiẹ̀ dá ẹ̀ṣẹ̀ kankan.’+

 7 Èèyàn míì wo ló dà bíi Jóòbù,

Tó ń mu ẹ̀gàn bí ẹni mu omi?

 8 Ó ń bá àwọn aṣebi kẹ́gbẹ́,

Ó sì ń bá àwọn èèyàn burúkú ṣe wọlé wọ̀de.+

 9 Torí o sọ pé, ‘Èèyàn kì í jèrè

Tó bá ń gbìyànjú láti ṣe ohun tí Ọlọ́run fẹ́.’+

10 Torí náà, ẹ fetí sí mi, ẹ̀yin tí ẹ ní òye:*

Ó dájú pé Ọlọ́run tòótọ́ kò ní hùwà burúkú,+

Pé Olódùmarè kò ní ṣe ohun tí kò dáa!+

11 Torí ó máa fi ohun tí èèyàn bá ṣe san án lẹ́san,+

Ó sì máa mú kó jèrè iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀.

12 Torí ó dájú pé, Ọlọ́run kì í hùwà burúkú;+

Olódùmarè kì í sì í yí ìdájọ́ po.+

13 Ta ló fi ayé sí ìkáwọ́ rẹ̀,

Ta ló sì fi ṣe olórí gbogbo ayé?*

14 Tó bá fiyè* sí wọn,

Tó bá kó ẹ̀mí àti èémí wọn jọ sọ́dọ̀ ara rẹ̀,+

15 Gbogbo èèyàn* jọ máa ṣègbé,

Aráyé á sì pa dà sí erùpẹ̀.+

16 Torí náà, tí o bá ní òye, fiyè sí èyí;

Fetí sí ọ̀rọ̀ mi dáadáa.

17 Ṣé ó yẹ kí ẹni tó kórìíra ìdájọ́ òdodo jẹ́ olórí,

Àbí o máa dá alágbára tó jẹ́ olódodo lẹ́bi?

18 Ṣé o máa sọ fún ọba pé, ‘O ò wúlò fún ohunkóhun,’

Àbí fún àwọn èèyàn pàtàkì pé, ‘Ẹni burúkú ni yín’?+

19 Ẹnì kan wà tí kì í ṣe ojúsàájú àwọn olórí,

Tí kì í sì í ka ọlọ́rọ̀ sí ju aláìní lọ,*+

Torí iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀ ni gbogbo wọn.+

20 Wọ́n lè kú lójijì,+ láàárín òru;+

Wọ́n gbọ̀n rìrì, wọ́n sì gbẹ́mìí mì;

A mú àwọn alágbára pàápàá kúrò, àmọ́ kì í ṣe iṣẹ́ ọwọ́ èèyàn.+

21 Torí ojú Ọlọ́run ń wo àwọn ọ̀nà èèyàn,+

Ó sì ń rí gbogbo ìṣísẹ̀ rẹ̀.

22 Kò sí òkùnkùn tàbí ibi tó ṣókùnkùn biribiri

Tí àwọn aṣebi máa fara pa mọ́ sí.+

23 Torí Ọlọ́run kò yan àkókò fún èèyàn kankan

Pé kó wá síwájú òun fún ìdájọ́.

24 Ó ń fọ́ àwọn alágbára túútúú láì ṣẹ̀ṣẹ̀ máa ṣèwádìí,

Ó sì ń fi àwọn míì rọ́pò wọn.+

25 Torí ó mọ ohun tí wọ́n ń ṣe;+

Ó ń bì wọ́n ṣubú ní òru, wọ́n sì pa run.+

26 Ó kọ lù wọ́n torí ìwà burúkú wọn,

Níbi tí gbogbo ojú ti lè rí i,+

27 Torí wọ́n ti yí pa dà, wọn ò tẹ̀ lé e mọ́,+

Wọn ò sì ka àwọn ọ̀nà rẹ̀ sí;+

28 Wọ́n mú kí àwọn aláìní ké pè é,

Tó fi gbọ́ igbe àwọn tí kò ní olùrànlọ́wọ́.+

29 Tí Ọlọ́run bá dákẹ́, ta ló lè dá a lẹ́bi?

Tó bá fojú pa mọ́, ta ló lè rí i?

Ì báà jẹ́ sí orílẹ̀-èdè tàbí èèyàn, ibì kan náà ló máa já sí,

30 Kí ẹni tí kò mọ Ọlọ́run* má bàa ṣàkóso,+

Tàbí kó dẹkùn fún àwọn èèyàn.

31 Ṣé ẹnikẹ́ni máa sọ fún Ọlọ́run pé,

‘Mo ti jìyà, bó tiẹ̀ jẹ́ pé mi ò ṣẹ̀ rárá;+

32 Jẹ́ kí n mọ ohun tí mi ò mọ̀;

Tí mo bá ti ṣe ohunkóhun tí kò dáa, mi ò ní ṣe bẹ́ẹ̀ mọ́’?

33 Ṣé ó máa san ọ́ lẹ́san bí o ṣe fẹ́, nígbà tó jẹ́ pé o kọ ìdájọ́ rẹ̀?

Ìwọ lo máa pinnu, kì í ṣe èmi.

Torí náà, sọ ohun tí o mọ̀ dáadáa fún mi.

34 Àwọn tó ní òye,* ọlọ́gbọ́n èyíkéyìí tó ń gbọ́ mi,

Máa sọ fún mi pé,

35 ‘Jóòbù ń sọ̀rọ̀ láìní ìmọ̀,+

Kò sì fi ìjìnlẹ̀ òye sọ̀rọ̀.’

36 Kí a* dán Jóòbù wò títí dé òpin,

Torí èsì rẹ̀ dà bíi ti àwọn èèyàn burúkú!

37 Ó fi ọ̀tẹ̀ kún ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀;+

Ó pàtẹ́wọ́ níwájú wa tẹ̀gàntẹ̀gàn,

Ó sì sọ̀rọ̀ púpọ̀ sí Ọlọ́run tòótọ́!”+

35 Élíhù ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ pé:

 2 “Ṣé ó dá ọ lójú pé o jàre tí wàá fi sọ pé,

‘Òdodo mi ju ti Ọlọ́run lọ’?+

 3 Torí o sọ pé, ‘Àǹfààní wo nìyẹn ṣe ọ́?*

Ṣé mo sàn ju ẹni tó dẹ́ṣẹ̀ lọ ni?’+

 4 Màá fún ọ lésì,

Màá sì fún àwọn ọ̀rẹ́ rẹ+ tó wà lọ́dọ̀ rẹ lésì.

 5 Gbé ojú sókè ọ̀run, kí o sì wò,

Wo àwọsánmà,*+ tó wà lókè rẹ.

 6 Tí o bá ṣẹ̀, kí lo ṣe tó dùn ún?+

Tí àṣìṣe rẹ bá ń pọ̀ sí i, kí lo ṣe fún un?+

 7 Tí o bá jẹ́ olódodo, kí lo fún un;

Kí ló gbà lọ́wọ́ rẹ?+

 8 Èèyàn bíi tìẹ ni ìwà burúkú rẹ lè ṣàkóbá fún,

Ọmọ aráyé nìkan sì ni òdodo rẹ wà fún.

 9 Àwọn èèyàn máa ń ké jáde tí ìnira bá mu wọ́n lómi;

Wọ́n á kígbe kí wọ́n lè bọ́ lọ́wọ́ alágbára tó ń jẹ gàba lé wọn lórí.+

10 Àmọ́ ẹnì kankan ò sọ pé, ‘Ọlọ́run mi dà, Aṣẹ̀dá mi Atóbilọ́lá,+

Ẹni tó ń mú ká kọrin ní òru?’+

11 Ó ń kọ́ wa+ ju àwọn ẹranko orí ilẹ̀+ lọ,

Ó sì ń mú ká gbọ́n ju àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run lọ.

12 Àwọn èèyàn ń ké jáde, àmọ́ kò dáhùn,+

Torí ìgbéraga àwọn ẹni burúkú.+

13 Ó dájú pé Ọlọ́run kì í fetí sí igbe asán;*+

Olódùmarè kì í fiyè sí i.

14 Ká má tiẹ̀ wá sọ ti àròyé tí ò ń ṣe pé o kò rí i!+

Ẹjọ́ rẹ wà níwájú rẹ̀, torí náà dúró dè é, kí o sì máa retí rẹ̀.+

15 Torí kò fi ìbínú pè ọ́ láti wá jíhìn;

Bẹ́ẹ̀ ni kò ka ìwàǹwára rẹ tó le gan-an sí.+

16 Jóòbù kàn ń la ẹnu lásán ni;

Ó sọ̀rọ̀ púpọ̀ láìní ìmọ̀.”+

36 Élíhù ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ pé:

 2 “Ní sùúrù fún mi díẹ̀ sí i kí n lè ṣàlàyé,

Torí mo ṣì ní ohun tí mo fẹ́ gbẹnu sọ fún Ọlọ́run.

 3 Màá sọ̀rọ̀ dáadáa nípa ohun tí mo mọ̀,

Màá sì ka Aṣẹ̀dá mi sí olódodo.+

 4 Ó dájú pé àwọn ọ̀rọ̀ mi kì í ṣe irọ́;

Ẹni tí ìmọ̀ rẹ̀ pé+ nìyí níwájú rẹ.

 5 Lóòótọ́, Ọlọ́run lágbára,+ kì í sì í kọ ẹnì kankan sílẹ̀;

Agbára òye* rẹ̀ pọ̀ gan-an.

 6 Kò ní dá ẹ̀mí àwọn ẹni burúkú sí,+

Àmọ́ ó ń dá ẹjọ́ àwọn tí ìyà ń jẹ bó ṣe tọ́.+

 7 Kì í gbé ojú rẹ̀ kúrò lára àwọn olódodo;+

Ó ń fi wọ́n sórí ìtẹ́ pẹ̀lú àwọn ọba,*+ ó sì gbé wọn ga títí láé.

 8 Àmọ́ tí a bá fi ṣẹkẹ́ṣẹkẹ̀ dè wọ́n,

Tí a sì fi okùn ìpọ́njú dè wọ́n,

 9 Ó ń fi ohun tí wọ́n ṣe hàn wọ́n,

Ẹ̀ṣẹ̀ tí ìgbéraga mú kí wọ́n dá.

10 Ó ń ṣí etí wọn kí wọ́n lè gba ìtọ́sọ́nà,

Ó sì ń sọ fún wọn pé kí wọ́n yí pa dà kúrò nínú ìwà burúkú.+

11 Tí wọ́n bá ṣègbọràn tí wọ́n sì sìn ín,

Nǹkan á máa lọ dáadáa fún wọn jálẹ̀ ọjọ́ ayé wọn,

Àwọn ọdún wọn á sì dùn.+

12 Àmọ́ tí wọn ò bá ṣègbọràn, idà* máa pa wọ́n run,+

Wọ́n sì máa kú láìní ìmọ̀.

13 Àwọn tí kò mọ Ọlọ́run* nínú ọkàn wọn máa ń di ìbínú sínú.

Wọn kì í kígbe fún ìrànlọ́wọ́ kódà nígbà tó bá dè wọ́n.

14 Wọ́n kú* ní kékeré,+

Ọ̀dọ̀ àwọn aṣẹ́wó ọkùnrin inú tẹ́ńpìlì ni wọ́n ti lo ìgbésí ayé wọn.*+

15 Àmọ́ Ọlọ́run* máa ń gba àwọn tí ìyà ń jẹ sílẹ̀;

Ó ń ṣí etí wọn nígbà tí wọ́n ń ni wọ́n lára.

16 Ó ń fà ọ́ kúrò ní bèbè ìdààmú+

Wá sí ibi tó fẹ̀, tí kò sí ìdílọ́wọ́,+

Tí oúnjẹ tó dọ́ṣọ̀ ti wà lórí tábìlì rẹ láti tù ọ́ nínú.+

17 Ìdájọ́ tó máa dé sórí ẹni burúkú máa wá tẹ́ ọ lọ́rùn,+

Nígbà tí a bá ṣèdájọ́ tí òdodo sì lékè.

18 Àmọ́ rí i pé ìbínú ò sún ọ ṣe ìkà,*+

Má sì jẹ́ kí àbẹ̀tẹ́lẹ̀ gọbọi ṣì ọ́ lọ́nà.

19 Ṣé igbe tí ò ń ké fún ìrànlọ́wọ́,

Tàbí gbogbo bí o ṣe ń sapá gidigidi lè gbà ọ́ lọ́wọ́ wàhálà?+

20 Má ṣe retí òru,

Tí àwọn èèyàn kì í sí ní àyè wọn.

21 Ṣọ́ra kí o má lọ hùwà àìtọ́,

Kí o wá yan èyí dípò ìyà.+

22 Wò ó! A gbé Ọlọ́run ga nínú agbára rẹ̀;

Olùkọ́ wo ló dà bíi rẹ̀?

23 Ta ló ń darí ọ̀nà rẹ̀,*+

Tàbí tó lè sọ fún un pé, ‘Ohun tí o ṣe ò dáa’?+

24 Rántí gbé iṣẹ́ rẹ̀ ga,+

Èyí tí àwọn èèyàn fi kọrin.+

25 Gbogbo aráyé ti rí i,

Ẹni kíkú ń wò ó láti ọ̀ọ́kán.

26 Àní, Ọlọ́run tóbi ju bí a ṣe lè mọ̀;+

Iye àwọn ọdún rẹ̀ kọjá òye wa.*+

27 Ó ń fa àwọn ẹ̀kán omi sókè;+

Omi inú àwọsánmà* rẹ̀ ń di òjò;

28 Àwọsánmà* wá rọ òjò;+

Ó rọ̀ sórí aráyé.

29 Ṣé ẹnikẹ́ni lè lóye àwọn ìpele ìkùukùu,*

Ààrá tó ń sán láti àgọ́* rẹ̀?+

30 Wo bó ṣe na mànàmáná*+ rẹ̀ sórí rẹ̀,

Tó sì bo ìsàlẹ̀* òkun mọ́lẹ̀.

31 Ó ń fi èyí bójú tó* àwọn èèyàn;

Ó ń fún wọn ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ oúnjẹ.+

32 Ó fi ọwọ́ rẹ̀ bo mànàmáná,

Ó sì dojú rẹ̀ kọ ohun tó fojú sùn.+

33 Ààrá rẹ̀ ń sọ̀rọ̀ rẹ̀,

Ẹran ọ̀sìn pàápàá ń sọ ẹni* tó ń bọ̀.

37 “Èyí mú kí ọkàn mi lù kìkì,

Ó sì ń fò sókè láti àyè rẹ̀.

 2 Ẹ fara balẹ̀ tẹ́tí sí ohùn rẹ̀ tó ń kù rìrì,

Àti ààrá tó ń ti ẹnu rẹ̀ jáde.

 3 Ó ń tú u jáde lábẹ́ gbogbo ọ̀run,

Ó sì ń rán mànàmáná+ rẹ̀ lọ dé àwọn ìkángun ayé.

 4 Lẹ́yìn náà ni ìró tó ń bú ramúramù;

Ó ń fi ohùn tó ga lọ́lá sán ààrá,+

Kì í sì í dá a dúró tí wọ́n bá gbọ́ ohùn rẹ̀.

 5 Ọlọ́run ń fi ohùn rẹ̀ sán ààrá+ lọ́nà àgbàyanu;

Ó ń ṣe àwọn ohun ńlá tí kò lè yé wa.+

 6 Nítorí ó sọ fún yìnyín pé, ‘Rọ̀ sórí ayé,’+

Ó sì sọ fún ọ̀wààrà òjò pé, ‘Rọ̀ sílẹ̀ rẹpẹtẹ.’+

 7 Ọlọ́run fòpin sí gbogbo ohun tí èèyàn ń ṣe,*

Kí gbogbo ẹni kíkú lè mọ iṣẹ́ ọwọ́ Rẹ̀.

 8 Àwọn ẹran igbó lọ sí ibùba wọn,

Wọn ò sì kúrò ní ibùgbé wọn.

 9 Ìjì ń fẹ́ wá láti àyè rẹ̀,+

Òtútù sì ń wá látinú atẹ́gùn àríwá.+

10 Èémí Ọlọ́run ń mú kí omi dì,+

Omi tó lọ salalu sì máa ń dì gbagidi.+

11 Àní, ó fi ìrì sínú àwọsánmà* kó lè wúwo;

Ó fọ́n ìmọ́lẹ̀ rẹ̀ ká+ sínú àwọsánmà;*

12 Wọ́n ń lọ yí ká sáwọn ibi tó ń darí wọn sí;

Wọ́n ń ṣe gbogbo ohun tó bá pa láṣẹ+ fún wọn lórí ilẹ̀ ayé tí à ń gbé.*

13 Ì báà jẹ́ torí ìyà*+ tàbí torí ilẹ̀ náà,

Tàbí torí ìfẹ́ tí kì í yẹ̀, ó ń mú kó wáyé.+

14 Fetí sí èyí, Jóòbù;

Dúró, kí o sì fara balẹ̀ ronú nípa àwọn iṣẹ́ àgbàyanu Ọlọ́run.+

15 Ṣé o mọ bí Ọlọ́run ṣe ń darí* àwọsánmà*

Àti bó ṣe ń mú kí mànàmáná kọ yẹ̀rì látinú àwọsánmà* rẹ̀?

16 Ṣé o mọ bí àwọsánmà* ṣe ń léfòó?+

Àwọn iṣẹ́ àgbàyanu Ẹni tí ìmọ̀ rẹ̀ pé nìyí.+

17 Kí ló dé tí aṣọ rẹ ń gbóná,

Nígbà tí afẹ́fẹ́ gúúsù mú kí ayé dúró jẹ́ẹ́?+

18 Ṣé ìwọ, pẹ̀lú rẹ̀, lè na òfúrufú jáde,*+

Kó dúró gbagidi bíi dígí onírin?

19 Sọ fún wa, ohun tí a máa sọ fún un;

A ò lè fèsì torí inú òkùnkùn la wà.

20 Ṣé ó yẹ ká sọ fún un pé mo fẹ́ sọ̀rọ̀ ni?

Àbí ẹnì kankan sọ̀rọ̀ tó yẹ ká lọ sọ fún un?+

21 Wọn ò lè rí ìmọ́lẹ̀* pàápàá,

Bó tiẹ̀ mọ́lẹ̀ yòò lójú ọ̀run,

Títí atẹ́gùn fi kọjá tó sì fẹ́ ìkùukùu* lọ.

22 Iyì tó ń tàn bíi wúrà jáde wá láti àríwá;

Ògo Ọlọ́run+ yẹ ní ohun tí à ń bẹ̀rù.

23 Ó kọjá agbára wa láti lóye Olódùmarè;+

Agbára rẹ̀ pọ̀ gan-an,+

Kì í ṣe ohun tó lòdì sí ìdájọ́ òdodo+ rẹ̀ àti òdodo rẹ̀ tó pọ̀ gidigidi.+

24 Torí náà, ó yẹ kí àwọn èèyàn bẹ̀rù rẹ̀.+

Torí kì í ṣe ojúure sí ẹnikẹ́ni tó gbọ́n lójú ara rẹ̀.”*+

38 Jèhófà wá dá Jóòbù lóhùn látinú ìjì,+ ó ní:

 2 “Ta lẹni yìí tí kò jẹ́ kí ìmọ̀ràn mi ṣe kedere,

Tó ń sọ̀rọ̀ láìní ìmọ̀?+

 3 Jọ̀ọ́, gbára dì, kí o ṣe bí ọkùnrin;

Màá bi ọ́ ní ìbéèrè, kí o sì dá mi lóhùn.

 4 Ibo lo wà nígbà tí mo fi ìpìlẹ̀ ayé sọlẹ̀?+

Sọ fún mi, tí o bá rò pé o mọ̀ ọ́n.

 5 Ta ló díwọ̀n rẹ̀, tí o bá mọ̀ ọ́n,

Àbí ta ló na okùn ìdíwọ̀n sórí rẹ̀?

 6 Inú ibo ni a ri àwọn ìtẹ́lẹ̀ rẹ̀ mọ́,

Àbí ta ló fi òkúta igun ilé rẹ̀ lélẹ̀,+

 7 Nígbà tí àwọn ìràwọ̀ òwúrọ̀+ jọ fayọ̀ ké jáde,

Tí gbogbo àwọn ọmọ Ọlọ́run*+ sì bẹ̀rẹ̀ sí í hó yèè, tí wọ́n ń yìn ín?

 8 Ta ló sì fi àwọn ilẹ̀kùn sé òkun,+

Nígbà tó tú jáde látinú ikùn,*

 9 Nígbà tí mo fi ìkùukùu wọ̀ ọ́ láṣọ,

Tí mo sì fi ìṣúdùdù tó kàmàmà wé e,

10 Nígbà tí mo pààlà ibi tí mo fẹ́ kó dé,

Tí mo sì fi àwọn ọ̀pá àtàwọn ilẹ̀kùn rẹ̀ sáyè wọn,+

11 Mo sì sọ pé, ‘Ibi tí o lè dé nìyí, má kọjá ibẹ̀;

Ìgbì rẹ tó ń ru sókè kò ní kọjá ibí yìí’?+

12 Ṣé o ti pàṣẹ fún òwúrọ̀ rí,*

Àbí o ti mú kí ilẹ̀ tó ń mọ́ bọ̀ mọ àyè rẹ̀,+

13 Láti di àwọn ìkángun ayé mú,

Kó sì gbọn àwọn ẹni burúkú dà nù kúrò nínú rẹ̀?+

14 Ó yí pa dà bí amọ̀ tí a gbé èdìdì lé,

Àwọn ohun tó wà nínú rẹ̀ sì ṣe kedere bíi ti ara aṣọ.

15 Àmọ́ a mú ìmọ́lẹ̀ àwọn ẹni burúkú kúrò,

A sì kán apá wọn tí wọ́n gbé sókè.

16 Ṣé o ti sọ̀ kalẹ̀ lọ sí àwọn orísun òkun,

Àbí o ti lọ káàkiri inú ibú omi?+

17 Ṣé a ti fi àwọn ẹnubodè ikú+ hàn ọ́ rí,

Àbí o ti rí àwọn ẹnubodè òkùnkùn biribiri?*+

18 Ǹjẹ́ o mọ bí ayé ṣe tóbi tó?+

Sọ fún mi, tí o bá mọ gbogbo èyí.

19 Apá ibo ni ìmọ́lẹ̀ ń gbé?+

Ibo sì ni òkùnkùn wà,

20 Tí o fi máa mú un lọ sí ilẹ̀ rẹ̀,

Tí wàá sì mọ àwọn ọ̀nà tó lọ sí ilé rẹ̀?

21 Ṣé o mọ èyí torí pé wọ́n ti bí ọ,

Tí iye ọdún* rẹ sì pọ̀ gan-an?

22 Ṣé o ti wọ àwọn ibi tí mo kó yìnyín jọ sí,+

Àbí o ti rí àwọn ibi tí mo kó òkúta yìnyín jọ sí,+

23 Èyí tí mo tọ́jú de ìgbà wàhálà,

De ọjọ́ ìjà àti ogun?+

24 Apá ibo ni ìmọ́lẹ̀* ti ń jáde wá,

Ibo sì ni atẹ́gùn ìlà oòrùn ti ń fẹ́ wá sí ayé?+

25 Ta ló la ọ̀nà fún àkúnya omi,

Tó sì la ọ̀nà fún ìjì tó ń sán ààrá látojú ọ̀run,+

26 Kí òjò lè rọ̀ síbi tí èèyàn kankan ò gbé,

Sí aginjù níbi tí kò sí èèyàn kankan,+

27 Kó lè tẹ́ ilẹ̀ tó ti di ahoro lọ́rùn,

Kó sì mú kí koríko hù?+

28 Ǹjẹ́ òjò ní bàbá,+

Ta sì ni bàbá ìrì tó ń sẹ̀?+

29 Látinú ilé ọlẹ̀ ta ni yìnyín ti jáde,

Ta ló sì bí yìnyín wínníwínní ojú ọ̀run,+

30 Nígbà tó dà bíi pé òkúta ló bo omi,

Tí ojú ibú omi sì dì gbagidi?+

31 Ṣé o lè so àwọn okùn àgbájọ ìràwọ̀ Kímà,*

Àbí o lè tú àwọn okùn àgbájọ ìràwọ̀ Késílì?*+

32 Ṣé o lè kó àgbájọ ìràwọ̀* jáde ní àsìkò rẹ̀,

Àbí o lè darí àgbájọ ìràwọ̀ Ááṣì* pẹ̀lú àwọn ọmọ rẹ̀?

33 Ṣé o mọ àwọn òfin tó ń darí ojú ọ̀run,+

Àbí o lè fipá mú kí ayé tẹ̀ lé àwọn àṣẹ wọn?*

34 Ṣé o lè ké sí ìkùukùu

Pé kó mú kí àkúnya omi bò ọ́ mọ́lẹ̀?+

35 Ṣé o lè rán mànàmáná jáde?

Ṣé wọ́n á wá sọ fún ọ pé, ‘Àwa rèé!’

36 Ta ló fi ọgbọ́n sínú àwọn ìkùukùu,*+

Àbí ta ló fún àwọn ohun tó wà lójú ọ̀run* ní òye?+

37 Ta ló gbọ́n débi tó fi lè ka àwọn ìkùukùu,*

Àbí ta ló lè da omi inú àwọn ìṣà omi ojú ọ̀run,+

38 Tí eruku bá kóra jọ,

Tí àwọn ìṣùpọ̀ iyẹ̀pẹ̀ sì lẹ̀ mọ́ra?

39 Ṣé o lè ṣọdẹ ẹran fún kìnnìún,

Àbí kí o fi oúnjẹ tẹ́ àwọn ọmọ kìnnìún lọ́rùn,+

40 Tí wọ́n bá dùbúlẹ̀ sínú ilé wọn,

Tàbí tí wọ́n lúgọ sínú ibùba wọn?

41 Ta ló ń pèsè oúnjẹ fún ẹyẹ ìwò,+

Tí àwọn ọmọ rẹ̀ bá ń ké jáde sí Ọlọ́run fún ìrànlọ́wọ́,

Tí wọ́n sì ń rìn kiri torí wọn ò rí nǹkan jẹ?

39 “Ṣé o mọ ìgbà tí àwọn ewúrẹ́ orí òkè máa ń bímọ?+

Ṣé o ti rí àgbọ̀nrín tó ń bímọ rí?+

 2 Ṣé o máa ń ka iye oṣù tí wọ́n máa ń lò?

Ṣé o mọ ìgbà tí wọ́n ń bímọ?

 3 Wọ́n máa ń bẹ̀rẹ̀ mọ́lẹ̀ tí wọ́n bá ń bímọ,

Ìrora ìrọbí wọn á sì lọ.

 4 Àwọn ọmọ wọn máa wá lágbára, wọ́n á sì dàgbà nínú pápá gbalasa;

Wọ́n á jáde lọ, wọn ò sì ní pa dà sọ́dọ̀ wọn mọ́.

 5 Ta ló tú kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ igbó* sílẹ̀ lómìnira,+

Ta ló sì tú okùn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ igbó?

 6 Mo ti fi aṣálẹ̀ tó tẹ́jú ṣe ilé rẹ̀,

Mo sì ti fi ilẹ̀ iyọ̀ ṣe ibùgbé rẹ̀.

 7 Ó ń pẹ̀gàn rúkèrúdò tó wà nínú ìlú;

Kò sì gbọ́ ariwo darandaran.

 8 Ó ń rìn kiri lórí àwọn òkè, ó ń wá ibi ìjẹko,

Ó ń wá gbogbo ewéko tútù.

 9 Ṣé akọ màlúù igbó máa fẹ́ sìn ọ́?+

Ṣé ó máa sun ilé ẹran* rẹ mọ́jú?

10 Ṣé o lè fi okùn fa akọ màlúù igbó láàárín poro,

Àbí ó lè tẹ̀ lé ọ lọ túlẹ̀* ní àfonífojì?

11 Ṣé o lè fọkàn tán agbára ńlá rẹ̀,

Kí o sì jẹ́ kó bá ọ ṣe iṣẹ́ alágbára?

12 Ṣé o máa gbára lé e pé kó gbé irè oko* rẹ wá,

Ṣé ó sì máa kó o jọ sí ibi ìpakà rẹ?

13 Ògòǹgò ń fi ayọ̀ lu ìyẹ́ rẹ̀ pìpì,

Àmọ́ ṣé a lè fi àwọn ìyẹ́ tó fi ń fò àti ìyẹ́ tó bo ara rẹ̀ wé ti ẹyẹ àkọ̀?+

14 Torí ilẹ̀ ló máa ń fi ẹyin rẹ̀ sí,

Ó sì ń mú kí wọ́n móoru nínú iyẹ̀pẹ̀.

15 Ó gbàgbé pé àwọn ẹsẹ̀ kan lè tẹ̀ wọ́n fọ́,

Tàbí pé ẹran igbó lè tẹ̀ wọ́n mọ́lẹ̀.

16 Ó ń ṣe àwọn ọmọ rẹ̀ ṣúkaṣùka, bí ẹni pé òun kọ́ ló bí wọn;+

Kò bẹ̀rù pé làálàá òun lè já sí asán.

17 Torí Ọlọ́run ò fún un ní* ọgbọ́n,

Kò sì pín òye kankan fún un.

18 Àmọ́ tó bá dìde tó sì gbọn ìyẹ́ rẹ̀ pìpì,

Ó máa fi ẹṣin àti ẹni tó gùn ún rẹ́rìn-ín.

19 Ṣé ìwọ lo fún ẹṣin ní agbára?+

Àbí ìwọ lo fi irun* tó ń fẹ́ lẹ́lẹ́ wọ ọrùn rẹ̀ láṣọ?

20 Ṣé o lè mú kó fò sókè bíi tata?

Bó ṣe ń fọn imú rẹ̀ lọ́nà tó gbayì ń kó jìnnìjìnnì báni.+

21 Ó ń fi àtẹ́lẹsẹ̀ talẹ̀ ní àfonífojì, ó sì ń bẹ́ tagbára-tagbára;+

Ó ń lọ tààràtà sójú ogun.*+

22 Ó rí ìbẹ̀rù, ó rẹ́rìn-ín, ohunkóhun ò sì já a láyà.+

Kì í torí idà yíjú pa dà.

23 Apó ń mì pẹkẹpẹkẹ sí i,

Ọ̀kọ̀ àti ẹ̀ṣín ń tàn yanran.

24 Bí ara rẹ̀ ṣe ń yá gágá, tó sì ń gbọn ara nù, ó ń bẹ́ gìjà síwájú,*

Kò lè dúró jẹ́ẹ́* tí wọ́n bá fun ìwo.

25 Tí ìwo bá dún, á figbe ta!

Ó ń gbóòórùn ìjà láti òkèèrè,

Ó sì ń gbọ́ ariwo àwọn ọ̀gágun àti igbe ogun.+

26 Ṣé òye rẹ ló ń mú kí àṣáǹwéwé fò lọ sókè réré,

Tó sì ń na ìyẹ́ rẹ̀ sí apá gúúsù?

27 Àbí ìwọ lò ń pàṣẹ fún idì, tó fi ń fò lọ sókè,+

Tó ń kọ́ ìtẹ́ rẹ̀ síbi tó ga fíofío,+

28 Tó ń sun orí òkè tó dà gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ mọ́jú,

Tó ń gbé ibi ààbò rẹ̀ níbi àpáta gbágungbàgun?*

29 Látibẹ̀ ló ti ń wá oúnjẹ;+

Ojú rẹ̀ ń ríran jìnnà réré.

30 Àwọn ọmọ rẹ̀ ń fa ẹ̀jẹ̀ mu;

Ibi tí òkú bá sì wà, ibẹ̀ ló máa ń wà.”+

40 Jèhófà ń fún Jóòbù lésì nìṣó pé:

 2 “Ṣó yẹ kí ẹni tó ń wá ẹ̀sùn bá Olódùmarè fa ọ̀rọ̀?+

Kí ẹni tó fẹ́ bá Ọlọ́run wí fèsì.”+

 3 Jóòbù dá Jèhófà lóhùn pé:

 4 “Wò ó! Mi ò já mọ́ nǹkan kan.+

Kí ni màá fi dá ọ lóhùn?

Mo fi ọwọ́ bo ẹnu mi.+

 5 Mo ti sọ̀rọ̀ lẹ́ẹ̀kan, àmọ́ mi ò ní dáhùn mọ́;

Lẹ́ẹ̀kejì, mi ò sì ní sọ̀rọ̀ mọ́.”

6 Ni Jèhófà bá dá Jóòbù lóhùn látinú ìjì, ó ní:+

 7 “Jọ̀ọ́, gbára dì, kí o ṣe bí ọkùnrin;

Màá bi ọ́ ní ìbéèrè, kí o sì dá mi lóhùn.+

 8 Ṣé o máa sọ pé mi ò ṣèdájọ́ bó ṣe tọ́ ni?*

Ṣé o máa dá mi lẹ́bi kí o lè jàre?+

 9 Ṣé o ní apá tó lágbára bíi ti Ọlọ́run tòótọ́,+

Àbí ṣé ohùn rẹ lè sán ààrá bíi tirẹ̀?+

10 Jọ̀ọ́, fi ògo àti ọlá ńlá ṣe ara rẹ lọ́ṣọ̀ọ́;

Kí o sì fi iyì àti ẹwà wọ ara rẹ láṣọ.

11 Tú ìbínú rẹ tó ń ru jáde;

Wo gbogbo ẹni tó ń gbéra ga, kí o sì rẹ̀ wọ́n nípò wálẹ̀.

12 Wo gbogbo ẹni tó ń gbéra ga, kí o sì rẹ̀ wọ́n sílẹ̀,

Kí o sì tẹ àwọn ẹni burúkú mọ́lẹ̀ níbi tí wọ́n dúró sí.

13 Fi wọ́n pa mọ́ sínú erùpẹ̀;

Dè wọ́n* síbi tó fara sin,

14 Nígbà náà, èmi pàápàá á sọ fún ọ* pé,

Ọwọ́ ọ̀tún rẹ lè gbà ọ́ là.

15 Wò ó, Béhémótì* nìyí, tí mo dá bí mo ṣe dá ọ.

Ó ń jẹ koríko bí akọ màlúù.

16 Wo bí ìbàdí rẹ̀ ṣe lágbára

Àti bí àwọn iṣan ikùn rẹ̀ ṣe lágbára tó!

17 Ó ń mú kí ìrù rẹ̀ le bí igi kédárì;

A hun àwọn iṣan itan rẹ̀ pọ̀.

18 Àwọn egungun rẹ̀ dà bí ọ̀pá bàbà oníhò;

Apá àti ẹsẹ̀ rẹ̀ dà bí ọ̀pá irin tó lágbára.

19 Ó wà ní ipò kìíní* lára àwọn iṣẹ́ Ọlọ́run;

Aṣẹ̀dá rẹ̀ nìkan ló lè mú idà rẹ̀ sún mọ́ ọn.

20 Torí àwọn òkè ló ń pèsè oúnjẹ fún un,

Níbi tí gbogbo àwọn ẹran igbó ti ń ṣeré.

21 Ó dùbúlẹ̀ sábẹ́ àwọn igi lótọ́sì,

Lábẹ́ òjìji àwọn esùsú* níbi irà.

22 Àwọn igi lótọ́sì ṣíji bò ó,

Àwọn igi pọ́pílà tó wà ní àfonífojì sì yí i ká.

23 Tí odò bá ń ru gùdù, kì í bẹ̀rù.

Ọkàn rẹ̀ balẹ̀, bí Jọ́dánì+ tiẹ̀ ń ya lu ẹnu rẹ̀.

24 Ṣé ẹnikẹ́ni lè mú un tó bá ń wò,

Àbí kó fi ìwọ̀* kọ́ ọ ní imú?

41 “Ṣé o lè fi ìwọ ẹja mú Léfíátánì,*+

Àbí o lè fi okùn de ahọ́n rẹ̀ mọ́lẹ̀?

 2 Ṣé o lè ki okùn* bọ ihò imú rẹ̀,

Àbí o lè fi ìwọ̀* kọ́ ọ lẹ́nu?

 3 Ṣé ó máa bẹ̀ ọ́ gidigidi,

Àbí ó máa fi ohùn jẹ́ẹ́jẹ́ẹ́ bá ọ sọ̀rọ̀?

 4 Ṣé ó máa bá ọ dá májẹ̀mú,

Kí o lè sọ ọ́ di ẹrú rẹ títí láé?

 5 Ṣé o máa bá a ṣeré bí ẹyẹ,

Àbí o máa so okùn mọ́ ọn fún àwọn ọmọbìnrin rẹ kéékèèké?

 6 Ṣé àwọn ọlọ́jà máa fi gba pààrọ̀?

Ṣé wọ́n máa pín in láàárín àwọn oníṣòwò?

 7 Ṣé o lè fi ọ̀kọ̀*+ gún gbogbo awọ ara rẹ̀,

Àbí o lè fi àwọn ọ̀kọ̀ ìpẹja gún orí rẹ̀?

 8 Gbé ọwọ́ rẹ lé e;

O máa rántí ìjà náà, o ò sì ní ṣe bẹ́ẹ̀ mọ́ láé!

 9 Asán ni ìrètí èyíkéyìí tí o bá ní pé o máa kápá rẹ̀.

Tí o bá rí i lásán, ṣe ni jìnnìjìnnì á bò ọ́.*

10 Kò sí ẹni tó jẹ́ ru ú sókè.

Ta ló wá lè kò mí lójú?+

11 Ta ló kọ́kọ́ fún mi ní ohunkóhun tí màá fi san án pa dà fún un?+

Tèmi ni ohunkóhun tó wà lábẹ́ ọ̀run.+

12 Mi ò ní ṣàìsọ̀rọ̀ nípa apá àti ẹsẹ̀ rẹ̀,

Nípa agbára ńlá rẹ̀ àti ara rẹ̀ tí a dá lọ́nà ìyanu.

13 Ta ló ti bọ́ ohun tó bò ó lára?

Ta ló máa wọ ẹnu rẹ̀ tó là sílẹ̀?

14 Ta ló lè fipá ṣí àwọn ilẹ̀kùn ẹnu* rẹ̀?

Gbogbo eyín rẹ̀ ń dẹ́rù bani.

15 Àwọn ìpẹ́ tò lọ́wọ̀ọ̀wọ́ ní ẹ̀yìn rẹ̀,*

Wọ́n lẹ̀ mọ́ra pinpin.

16 Ọ̀kọ̀ọ̀kan lẹ̀ típẹ́típẹ́ mọ́ ìkejì,

Débi pé afẹ́fẹ́ kò lè wọ àárín wọn.

17 Wọ́n lẹ̀ mọ́ra wọn;

Wọ́n so mọ́ra wọn, wọn ò sì ṣeé yà sọ́tọ̀ọ̀tọ̀.

18 Ìró tó ń ti imú rẹ̀ jáde ń mú kí iná kọ yẹ̀rì,

Ojú rẹ̀ sì dà bí ìmọ́lẹ̀ àárọ̀ tó ń tàn.

19 Mànàmáná ń kọ yẹ̀rì láti ẹnu rẹ̀;

Iná ń ta pàrà jáde.

20 Èéfín ń tú jáde látinú ihò imú rẹ̀,

Bí iná ìléru tí wọ́n fi koríko etídò dáná sí.

21 Èémí rẹ̀ ń mú kí ẹyin iná jó,

Ọwọ́ iná sì ń ti ẹnu rẹ̀ jáde.

22 Ọrùn rẹ̀ lágbára gan-an,

Jìnnìjìnnì sì ń sá lọ níwájú rẹ̀.

23 Àwọn ìṣẹ́po ẹran ara rẹ̀ lẹ̀ mọ́ra pẹ́kípẹ́kí;

Wọ́n le gbagidi, bí ohun tí a rọ, tó dúró digbí.

24 Ọkàn rẹ̀ le bí òkúta,

Àní, ó le bí ìyá ọlọ.

25 Tó bá gbéra, ẹ̀rù máa ń ba àwọn alágbára pàápàá;

Tó bá jà pìtìpìtì, ṣìbáṣìbo á bá wọn.

26 Kò sí idà tó bà á tó lè ràn án;

Bẹ́ẹ̀ ni ọ̀kọ̀, igaga tàbí orí ọfà kò lè ràn án.+

27 Ó ka irin sí pòròpórò

Àti bàbà sí igi tó ti jẹrà.

28 Ọfà kò lè lé e lọ;

Òkúta kànnàkànnà máa ń di àgékù pòròpórò tó bá bà á.

29 Ó ka kùmọ̀ sí àgékù pòròpórò,

Ó sì ń fi ẹ̀ṣín rẹ́rìn-ín bó ṣe ń dún pẹkẹpẹkẹ.

30 Abẹ́ rẹ̀ dà bí àwọn àfọ́kù ìkòkò tó mú;

Ó tẹ́ ara rẹ̀ sínú ẹrọ̀fọ̀ bí ohun tí wọ́n fi ń pakà.+

31 Ó ń mú kí ibú hó bí ìkòkò;

Ó ń ru òkun gùdù bí ìkòkò òróró ìpara.

32 Ipa ọ̀nà rẹ̀ ń dán lẹ́yìn rẹ̀.

Ṣe ni èèyàn á rò pé ibú omi ní irun funfun.

33 Kò sí ohun tó dà bíi rẹ̀ ní ayé,

Ẹ̀dá tí a dá pé kó má bẹ̀rù ohunkóhun.

34 Ó ń fìbínú wo gbogbo ohun tó ń gbéra ga.

Òun ni ọba lórí gbogbo ẹran ńlá inú igbó.”

42 Lẹ́yìn náà, Jóòbù dá Jèhófà lóhùn pé:

 2 “Mo ti wá mọ̀ pé o lè ṣe ohun gbogbo

Àti pé kò sí ohun tó wà lọ́kàn rẹ tí kò ní ṣeé ṣe fún ọ.+

 3 O sọ pé, ‘Ta lẹni yìí tí kò jẹ́ kí ìmọ̀ràn mi ṣe kedere, tí kò ní ìmọ̀?’+

Torí náà, mo sọ̀rọ̀, àmọ́ mi ò lóye,

Nípa àwọn ohun tó yà mí lẹ́nu gidigidi, tí mi ò mọ̀.+

 4 O sọ pé, ‘Jọ̀ọ́ fetí sílẹ̀, màá sì sọ̀rọ̀.

Màá bi ọ́ ní ìbéèrè, kí o sì dá mi lóhùn.’+

 5 Etí mi ti gbọ́ nípa rẹ,

Àmọ́ ní báyìí, mo ti fi ojú mi rí ọ.

 6 Ìdí nìyẹn tí mo fi kó ọ̀rọ̀ mi jẹ,*+

Mo sì ronú pìwà dà nínú iyẹ̀pẹ̀ àti eérú.”+

7 Lẹ́yìn tí Jèhófà bá Jóòbù sọ àwọn ọ̀rọ̀ yìí, Jèhófà sọ fún Élífásì ará Témánì pé:

“Inú ń bí mi gidigidi sí ìwọ àtàwọn ọ̀rẹ́ rẹ méjèèjì,+ torí ẹ ò sọ òtítọ́ nípa mi,+ bí ìránṣẹ́ mi Jóòbù ṣe sọ òtítọ́. 8 Ó yá, ẹ mú akọ màlúù méje àti àgbò méje, kí ẹ lọ bá Jóòbù ìránṣẹ́ mi, kí ẹ sì rú ẹbọ sísun fún ara yín. Jóòbù ìránṣẹ́ mi sì máa gbàdúrà fún yín.+ Ó dájú pé màá gbọ́ ẹ̀bẹ̀ rẹ̀* pé kí n má fìyà jẹ yín nítorí ìwà òmùgọ̀ yín, torí ẹ ò sọ òtítọ́ nípa mi, bí ìránṣẹ́ mi Jóòbù ṣe sọ òtítọ́.”

9 Nítorí náà, Élífásì ará Témánì, Bílídádì ọmọ Ṣúáhì àti Sófárì ọmọ Náámà lọ ṣe ohun tí Jèhófà sọ fún wọn pé kí wọ́n ṣe. Jèhófà sì gbọ́ àdúrà Jóòbù.

10 Lẹ́yìn tí Jóòbù gbàdúrà fún àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀,+ Jèhófà mú kí ìpọ́njú Jóòbù kúrò,+ ó sì dá ọlá rẹ̀ pa dà.* Jèhófà fún un ní ìlọ́po méjì ohun tó ní tẹ́lẹ̀.+ 11 Gbogbo àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin rẹ̀ àti gbogbo àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ tẹ́lẹ̀+ wá sọ́dọ̀ rẹ̀, wọ́n sì bá a jẹun nínú ilé rẹ̀. Wọ́n bá a kẹ́dùn, wọ́n sì tù ú nínú torí gbogbo àjálù tí Jèhófà fàyè gbà kó dé bá a. Ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn fún un ní ẹyọ owó àti òrùka wúrà.

12 Jèhófà wá bù kún ìgbẹ̀yìn ayé Jóòbù ju ti ìbẹ̀rẹ̀ lọ,+ Jóòbù wá ní ẹgbẹ̀rún mẹ́rìnlá (14,000) àgùntàn, ẹgbẹ̀rún mẹ́fà (6,000) ràkúnmí, màlúù méjì-méjì lọ́nà ẹgbẹ̀rún (1,000) àti ẹgbẹ̀rún (1,000) abo kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́.+ 13 Ó tún wá bí ọmọkùnrin méje míì àti ọmọbìnrin mẹ́ta míì.+ 14 Ó pe orúkọ ọmọbìnrin àkọ́kọ́ ní Jẹ̀mímà, ìkejì ní Kẹsáyà àti ìkẹta ní Kereni-hápúkì. 15 Ní gbogbo ilẹ̀ náà, kò sí obìnrin kankan tó rẹwà bí àwọn ọmọbìnrin Jóòbù, bàbá wọn sì fún wọn ní ogún pẹ̀lú àwọn arákùnrin wọn.

16 Lẹ́yìn èyí, Jóòbù lo ogóje (140) ọdún sí i láyé, ó sì rí àwọn ọmọ rẹ̀ àti àwọn ọmọ ọmọ rẹ̀, dé ìran kẹrin. 17 Nígbẹ̀yìn-gbẹ́yín, Jóòbù kú. Ó pẹ́ láyé, ayé rẹ̀ sì dáa.*

Ó ṣeé ṣe kó túmọ̀ sí “Ohun Ìkórìíra.”

Tàbí “Aláìlẹ́bi àti adúróṣinṣin.”

Ní Héb., “màlúù méjì-méjì lọ́nà ọgọ́rùn-ún márùn-ún.”

Ní Héb., “abo kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́.”

Tàbí “ní ilé ọ̀kọ̀ọ̀kan lọ́jọ́ tó bá yí kàn án.”

Àkànlò èdè Hébérù tó ń tọ́ka sí àwọn áńgẹ́lì gẹ́gẹ́ bí ọmọ Ọlọ́run.

Ní Héb., “fi ọkàn rẹ sí.”

Tàbí “Aláìlẹ́bi àti adúróṣinṣin.”

Tàbí “ní ìkáwọ́ rẹ.”

Ní Héb., “ní ojú.”

Tàbí kó jẹ́, “Mànàmáná wá.”

Tàbí “kò sì ka ohunkóhun tí kò tọ́ sí Ọlọ́run lọ́rùn.”

Àkànlò èdè Hébérù tó ń tọ́ka sí àwọn áńgẹ́lì gẹ́gẹ́ bí ọmọ Ọlọ́run.

Ní Héb., “fi ọkàn rẹ sí.”

Tàbí “Aláìlẹ́bi àti adúróṣinṣin.”

Ní Héb., “gbé e mì.”

Tàbí “ọkàn rẹ̀.”

Tàbí “ní ìkáwọ́ rẹ.”

Tàbí “ọkàn.”

Ní Héb., “ní ojú.”

Tàbí “àwọn ọgbẹ́ tó le gan-an.”

Tàbí “ojúlùmọ̀.”

Ní Héb., “gégùn-ún fún ọjọ́ rẹ̀.”

Tàbí “òkùnkùn àti òjìji ikú.”

Ohun tí a mọ̀ ọ́n sí ni ọ̀nì tàbí ẹran míì tó tóbi, tó lágbára, tó sì ń gbé inú omi.

Tàbí kó jẹ́, “kọ́ àwọn ibi tó ti di ahoro fún ara wọn.”

Tàbí “tí ọkàn wọn gbọgbẹ́.”

Ní Héb., “àárẹ̀ sì mú ọ.”

Tàbí “hùmọ̀.”

Tàbí “àwọn ọmọ kìnnìún tó tó ọdẹ ṣe (onígọ̀gọ̀).”

Tàbí “òjíṣẹ́.”

Tàbí “kòkòrò.”

Tàbí “máa bá ọ dá májẹ̀mú (ṣe àdéhùn).”

Ní Héb., “àlàáfíà ni àgọ́ rẹ.”

Tàbí “ọ̀rọ̀ tó le, tí mo sọ láìronú jinlẹ̀.”

Tàbí “Ọkàn mi.”

Tàbí “tí màá fi jẹ́ kí ẹ̀mí (ọkàn) mi gùn.”

Tàbí “Àwùjọ arìnrìn-àjò àwọn Sábéà.”

Ní Héb., “Ẹ rí ẹ̀rù àjálù mi.”

Ní Héb., “rà mí pa dà.”

Tàbí “aláìníbaba.”

Tàbí “fi ọ̀rẹ́ yín gba pààrọ̀.”

Tàbí “títí di àfẹ̀mọ́jú.”

Ní Héb., “ohun rere.”

Tàbí “Ṣìọ́ọ̀lù,” ìyẹn ibojì aráyé. Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.

Tàbí “ọgbẹ́ ọkàn.”

Tàbí “ọkàn mi.”

Ní Héb., “àwọn egungun mi.”

Ní Héb., “fi ọkàn rẹ sí i.”

Ní Héb., “Ó fi wọ́n lé ọ̀tẹ̀ wọn lọ́wọ́.”

Tàbí “ta ara rẹ̀ jí fún ọ.”

Ní Héb., “Kí wọ́n sì sọ̀rọ̀ látọkàn wá?”

Ìyẹn, koríko etí omi.

Ní Héb., “Báyìí ni ọ̀nà gbogbo àwọn tó gbàgbé Ọlọ́run.”

Tàbí “apẹ̀yìndà.”

Ní Héb., “ilé.”

Tàbí “Ó ń wo ilé olókùúta.”

Tàbí “gbé e mì.”

Tàbí “bí ọ̀nà rẹ̀ ṣe máa yọ́ nìyẹn.”

Tàbí “aláìlẹ́bi.”

Ní Héb., “di ọwọ́ àwọn ẹni ibi mú.”

Tàbí “mú Un lọ sílé ẹjọ́.”

Ní Héb., “Ó jẹ́ ọlọ́gbọ́n nínú ọkàn rẹ̀.”

Tàbí “mú àwọn òkè kúrò níbi tí wọ́n wà.”

Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ àgbájọ ìràwọ̀ Béárì Ńlá (ìyẹn, Ursa Major).

Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ àgbájọ ìràwọ̀ Óríónì.

Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ àwọn ìràwọ̀ Píléádésì ní àgbájọ ìràwọ̀ Taurus.

Ní Héb., “àwọn yàrá inú ní apá gúúsù.”

Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ ẹran ńlá kan nínú òkun.

Tàbí kó jẹ́, “ẹni tí mò ń bá ṣe ẹjọ́.”

Ní Héb., “pè mí lẹ́jọ́.”

Tàbí “Tí mi ò bá tiẹ̀ mọwọ́ mẹsẹ̀.”

Ní Héb., “pè mí ní oníwà wíwọ́.”

Tàbí “Tí mi ò bá tiẹ̀ mọwọ́ mẹsẹ̀.”

Tàbí “mi ò mọ ọkàn mi.”

Tàbí “Mo kórìíra ayé mi yìí; Mo kọ ayé mi yìí.”

Tàbí “àwọn tí kò fi ìwà títọ́ sílẹ̀.”

Iyẹn, koríko etí omi.

Ní Héb., “ẹni burúkú ni mí.”

Tàbí “ọṣẹ àwẹ̀dá.”

Tàbí “ṣe alárinà.”

Ní Héb., “gbé ọwọ́ rẹ̀ lé àwa méjèèjì.”

Ní Héb., “ó máa mú ọ̀pá rẹ̀ kúrò lára mi ni.”

Tàbí “Ọkàn mi.”

Tàbí “ọgbẹ́ ọkàn.”

Tàbí “èémí; ìwàláàyè.”

Ní Héb., “O sì ti fi àwọn nǹkan yìí pa mọ́ sínú ọkàn rẹ.”

Tàbí “inú mi lè dùn díẹ̀.”

Tàbí “ilẹ̀ òkùnkùn àti òjìji ikú.”

Tàbí “ṣé ẹni tó ń fọ́nnu máa jàre?”

Ní Héb., “ètè.”

Tàbí “mọ òpin.”

Tàbí “Ṣìọ́ọ̀lù,” ìyẹn ibojì aráyé. Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.

Tàbí “bá bí ọmọ rẹ̀ ní èèyàn.”

Tàbí “Ọkàn tó kú.”

Ní Héb., “ẹ̀yin ni àwọn èèyàn náà.”

Ní Héb., “ọkàn.”

Tàbí “tí ẹsẹ̀ wọn ń yọ̀.”

Tàbí kó jẹ́, “bá ayé sọ̀rọ̀.”

Tàbí “ọkàn gbogbo ẹni tó wà láàyè.”

Tàbí “èémí.”

Ní Héb., “gbogbo ẹran ara èèyàn.”

Ní Héb., “òkè ẹnu.”

Tàbí “láìsí nǹkan kan lára wọn.”

Tàbí “àwọn àgbààgbà.”

Ní Héb., “tú àmùrè àwọn alágbára.”

Ní Héb., “ọkàn.”

Tàbí “ṣe ojúsàájú sí i.”

Tàbí “ọ̀rọ̀ ìrántí.”

Ní Héb., “kókó rubutu orí apata yín.”

Ní Héb., “Kí ló dé tí mo fi eyín mi gbé ẹran ara mi?”

Tàbí “ọkàn.”

Tàbí “gbèjà ara mi.”

Tàbí “apẹ̀yìndà.”

Tàbí kó jẹ́, “Tí ẹnì kan bá ṣe bẹ́ẹ̀, màá dákẹ́, màá sì kú.”

Ní Héb., “Ohun méjì péré ni kí o má ṣe fún mi.”

Ní Héb., “ó,” ó ṣeé ṣe kó jẹ́ Jóòbù ló ń tọ́ka sí.

Tàbí “kòkòrò.”

Tàbí “ṣìbáṣìbo.”

Tàbí kó jẹ́, “a sì ké e kúrò.”

Ní Héb., “mi.”

Tàbí “Ṣìọ́ọ̀lù,” ìyẹn ibojì aráyé. Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.

Tàbí “O máa yán hànhàn fún.”

Tàbí “ọkàn rẹ̀.”

Tàbí “ìmọ̀ asán.”

Tàbí “Àṣìṣe rẹ ń kọ́ ẹnu rẹ.”

Ní Héb., “búrẹ́dì.”

Tàbí “fẹ́ borí.”

Ní Héb., “kókó rubutu tó nípọn lórí apata rẹ̀.”

Ìyẹn, ìrètí èyíkéyìí tó ní láti pa dà sí bó ṣe wà tẹ́lẹ̀.

Ní Héb., “rẹ̀.”

Tàbí “apẹ̀yìndà.”

Tàbí “ọ̀rọ̀ líle.”

Tàbí “Tí ọkàn yín bá wà ní ipò tí ọkàn mi wà.”

Tàbí “àwọn tó kóra jọ sọ́dọ̀ mi.”

Ní Héb., “aṣọ àpò ìdọ̀họ.”

Tàbí “okun.” Ní Héb., “ìwo.”

Tàbí “Òjìji ikú.”

Tàbí kó jẹ́, “Bí ojú mi ṣe ń wo Ọlọ́run, tí mi ò lè sùn.”

Tàbí “kí n tẹjú mọ́.”

Ní Héb., “àfipòwe.”

Tàbí “apẹ̀yìndà.”

Tàbí “Ṣìọ́ọ̀lù,” ìyẹn ibojì aráyé. Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.

Tàbí “sàréè.”

Ìyẹn, ìrètí mi.

Tàbí “Ṣìọ́ọ̀lù,” ìyẹn ibojì aráyé. Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.

Tàbí kó jẹ́, “aláìmọ́.”

Tàbí “ọkàn.”

Tàbí “tiro.”

Ní Héb., “Àkọ́bí ikú.”

Tàbí “ikú oró.”

Ní Héb., “Ohun tí kì í ṣe tirẹ̀.”

Ní Héb., “Orúkọ rẹ̀ ò sì ní sí.”

Tàbí “níbi tó ń gbé fúngbà díẹ̀.”

Tàbí “mú mi.” Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.

Tàbí “bú mi.”

Tàbí “Àwọn mọ̀lẹ́bí mi.”

Ní Héb., “àwọn ọmọ ilé ọlẹ̀ mi,” ìyẹn, ilé ọlẹ̀ tí mo tinú rẹ̀ jáde (ilé ọlẹ̀ ìyá mi).

Ní Héb., “Tí ẹran ara mi kò sì tẹ́ yín lọ́rùn?”

Tàbí “olùtúnrà.”

Ní Héb., “dìde lórí iyẹ̀pẹ̀.”

Ní Héb., “pa run.”

Tàbí “Àmọ́ àwọn kíndìnrín mi ti kọṣẹ́ nínú mi.”

Ní Héb., “Ẹ̀mí kan látinú òye mi.”

Tàbí “aráyé; Ádámù.”

Tàbí “apẹ̀yìndà.”

Ìyẹn, okun rẹ̀.

Tàbí “òróòro.”

Ní Héb., “Ahọ́n.”

Ní Héb., “kò sì ní gbé e mì.”

Ní Héb., “Ó.”

Ní Héb., “rẹ̀.”

Ní Héb., “ẹ̀mí mi.”

Tàbí “alágbára.”

Tàbí “fèrè ape.”

Tàbí “Ṣìọ́ọ̀lù,” ìyẹn ibojì aráyé. Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.

Tàbí “ní ìṣẹ́jú kan,” ìyẹn, ikú ìrọ̀rùn tí kò pẹ́ rárá.

Tàbí “Ìmọ̀ràn; Ète.”

Ìyẹn, èèpo fúlẹ́fúlẹ́ ara ọkà.

Tàbí “gé iye oṣù rẹ̀ sí méjì.”

Ní Héb., “fi ìmọ̀ kọ́ Ọlọ́run.”

Ní Héb., “Tí mùdùnmúdùn egungun rẹ̀ sì tutù.”

Tàbí “ọkàn ẹlòmíì gbọgbẹ́ títí tó fi kú.”

Tàbí kó jẹ́, “láti fi hùwà ipá sí mi.”

Ní Héb., “àwọn àmì wọn.”

Ní Héb., “Ó sì máa wọ́ gbogbo aráyé tẹ̀ lé e.”

Tàbí “ṣé ó ń múnú Olódùmarè dùn.”

Ní Héb., “bọ́ aṣọ àwọn tó wà ní ìhòòhò.”

Tàbí “aláìlóbìí.”

Ní Héb., “páńpẹ́ ẹyẹ.”

Tàbí “Ìkùukùu.”

Tàbí “òbìrìkìtì.”

Tàbí “tí a ké ẹ̀mí wọn kúrú.”

Ní Héb., “odò.”

Tàbí “wúrà kéékèèké.”

Tàbí “wúrà kéékèèké.”

Tàbí “ẹni tí ìbànújẹ́ dorí rẹ̀ kodò.”

Tàbí “ìṣọ̀tẹ̀ ni àròyé mi.”

Tàbí “ohun tó pa láṣẹ fún mi.”

Tàbí “Tí ọkàn rẹ̀.”

Tàbí “ohun tó ti pa láṣẹ.”

Ìyẹn, ọjọ́ ìdájọ́ rẹ̀.

Tàbí “aláìlóbìí.”

Tàbí “ìdógò.”

Tàbí kó jẹ́, “kórè oúnjẹ ẹran nínú oko.”

Ó túmọ̀ sí ṣíṣà lára irè oko tí wọ́n bá fi sílẹ̀.

Tàbí kó jẹ́, “Wọ́n ń fún òróró láàárín àwọn ògiri ilẹ̀ onípele.”

Tàbí “Ọkàn àwọn tó ṣèṣe.”

Tàbí kó jẹ́, “Ọlọ́run ò fi ẹ̀sùn kan ẹnikẹ́ni.”

Ní Héb., “dá ilé lu.”

Ní Héb., “Ó yára lórí omi.”

Tàbí “Ṣìọ́ọ̀lù,” ìyẹn ibojì aráyé. Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.

Ní Héb., “Ilé ọlẹ̀.”

Ní Héb., “Ó.”

Ní Héb., “Ó.”

Ní Héb., “àwọn ọ̀nà wọn.”

Ní Héb., “ibi gíga rẹ̀.”

Tàbí “ṣe lè mọ́.”

Tàbí “làákàyè rẹ.”

Tàbí “lọ́pọ̀ yanturu.”

Ní Héb., “Èémí (ẹ̀mí) ta ló sì ti ọ̀dọ̀ rẹ jáde?”

Tàbí “ti sọ di aláìlágbára.”

Tàbí “Ṣìọ́ọ̀lù,” ìyẹn ibojì aráyé. Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.

Ní Héb., “rẹ̀.”

Tàbí “Ábádónì.”

Ní Héb., “àríwá.”

Ní Héb., “òfìfo.”

Tàbí “ìkùukùu.”

Ní Héb., “Ó ṣe òbìrìkìtì.”

Ní Héb., “Ráhábù.”

Tàbí “atẹ́gùn.”

Tàbí “tó ń yára lọ.”

Ní Héb., “òwe.”

Tàbí “tó mú kí ọkàn mi gbọgbẹ́.”

Ní Héb., “ráhùn.”

Tàbí “Mi ò ní mú ìwà títọ́ mi kúrò lọ́dọ̀ mi; Mi ò ní jáwọ́ nínú ìwà títọ́ mi.”

Tàbí “kẹ́gàn mi.”

Tàbí “ní gbogbo ọjọ́ ayé mi.”

Tàbí “apẹ̀yìndà.”

Tàbí “ọkàn.”

Tàbí kó jẹ́, “nípasẹ̀ ọwọ́.”

Tàbí “kòkòrò.”

Tàbí kó jẹ́, “Wọ́n pàtẹ́wọ́ sí i, wọ́n sì súfèé sí i láti àyè wọn.”

Ní Héb., “da bàbà jáde.”

Ní Héb., “òkúta.”

Ó jọ pé bí wọ́n ṣe ń wa kùsà ló ń sọ.

Tàbí “tí wọ́n yọ́ mọ́.”

Ní Héb., “ìwọ̀n.”

Tàbí “àwọsánmà.”

Ní Héb., “òwe.”

Ní Héb., “ṣì wà ní àwọn ọjọ́ tí mo lókun.”

Tàbí “ìránṣẹ́.”

Ní Héb., “fara pa mọ́.”

Tàbí “aláìlóbìí.”

Tàbí “aṣọ àwọ̀lékè tí kò lápá.”

Ní Héb., “ìtẹ́ mi.”

Ní Héb., “kán sí wọn.”

Tàbí kó jẹ́, “Wọn ò mú kí ìmọ́lẹ̀ ojú mi ṣókùnkùn.”

Ní Héb., “nà wọ́n kúrò.”

Ní Héb., “àfipòwe.”

Ní Héb., “tú okùn ọrun mi.”

Tàbí “Wọ́n tú ìjánu kúrò.”

Tàbí kó jẹ́, “Láìsí ẹnikẹ́ni tó ń ràn wọ́n lọ́wọ́.”

Tàbí “ọkàn.”

Ní Héb., “Wọ́n dá egungun mi lu.”

Tàbí kó jẹ́, “Ìyà tó ń jẹ mí pọ̀ gan-an débi pé ó sọ mí dìdàkudà.”

Tàbí kó jẹ́, “fọ́ mi yángá.”

Ní Héb., “àwókù.”

Tàbí “tí ìnira ń bá lójúmọ́?”

Tàbí “ọkàn mi.”

Tàbí “akátá.”

Tàbí kó jẹ́, “Ibà.”

Tàbí “fèrè ape.”

Tàbí kó jẹ́, “pẹ̀lú àwọn aláìṣòótọ́ èèyàn.”

Tàbí “àwọn àtọmọdọ́mọ mi.”

Ní Héb., “kúnlẹ̀ sórí rẹ̀.”

Ní Héb., “iná ajẹnirun.”

Tàbí “fa gbòǹgbò èso mi pàápàá tu.”

Tàbí “pè mí lẹ́jọ́.”

Ní Héb., “nínú ilé ọlẹ̀.”

Ní Héb., “kí ojú opó kọṣẹ́.”

Ní Héb., “ó.”

Ní Héb., “rẹ̀.”

Ní Héb., “látinú ilé ọlẹ̀ ìyá mi.”

Ní Héb., “Tí abẹ́nú rẹ̀ kò.”

Tàbí kó jẹ́, “Nígbà tí mo rí i pé wọ́n tì mí lẹ́yìn ní ẹnubodè ìlú.”

Tàbí “ibi palaba èjìká.”

Tàbí “kúrò ní ojúhò rẹ̀; kúrò ní egungun òkè rẹ̀.”

Ní Héb., “ìmọ́lẹ̀ ń tàn.”

Tàbí “ọkàn.”

Ní Héb., “ẹran.”

Tàbí “àjèjì.”

Tàbí “Ìbuwọ́lùwé mi rèé.”

Tàbí “ọkàn àwọn.”

Tàbí “wíìtì.”

Tàbí “ó jẹ́ olódodo lójú ara rẹ̀.”

Tàbí “ọkàn òun.”

Ní Héb., “Mo kéré ní ọjọ́.”

Ní Héb., “àwọn ọjọ́.”

Tàbí “Ọ̀pọ̀ ọjọ́ nìkan kì í.”

Tàbí “bá Jóòbù wí.”

Tàbí “fún ẹnikẹ́ni ní orúkọ oyè.”

Ní Héb., “Ahọ́n mi pẹ̀lú òkè ẹnu mi.”

Ní Héb., “gbé èdìdì lé.”

Tàbí “ẹ̀mí.”

Tàbí “sàréè.”

Tàbí “ohun ìjà (ohun ọṣẹ́).”

Ní Héb., “ẹ̀mí rẹ̀.”

Tàbí “Tí ọkàn rẹ̀.”

Tàbí “hàn síta.”

Tàbí “Ẹ̀mí.”

Tàbí “sàréè.”

Tàbí “áńgẹ́lì.”

Tàbí “sàréè.”

Tàbí “le.”

Ní Héb., “kọrin.”

Tàbí kó jẹ́, “Mi ò sì jèrè.”

Tàbí “ẹ̀mí.”

Tàbí “sàréè.”

Tàbí “ọkàn rẹ̀.”

Tàbí “sàréè.”

Ní Héb., “òkè ẹnu.”

Ní Héb., “ọkàn.”

Tàbí “ayé tá à ń gbé.”

Ní Héb., “fọkàn.”

Ní Héb., “ẹran ara.”

Tàbí “ka èèyàn pàtàkì sí ju ẹni rírẹlẹ̀.”

Tàbí “apẹ̀yìndà.”

Ní Héb., “ọkàn.”

Tàbí kó jẹ́, “Bàbá mi, kí a.”

Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ Ọlọ́run ló ń tọ́ka sí.

Tàbí “ìkùukùu.”

Tàbí “irọ́.”

Ní Héb., “ọkàn.”

Tàbí kó jẹ́, “Ó ń fi àwọn ọba jẹ.”

Tàbí “ohun ìjà (ohun ọṣẹ́).”

Tàbí “Àwọn apẹ̀yìndà.”

Tàbí “Ọkàn wọn kú.”

Tàbí kó jẹ́, “parí ayé wọn.”

Ní Héb., “Ó.”

Tàbí “pàtẹ́wọ́ ìkà.”

Tàbí kó jẹ́, “ti yẹ ọ̀nà rẹ̀ wò; ti pè é kó wá jíhìn.”

Tàbí “Àwámáridìí ni iye àwọn ọdún rẹ̀.”

Tàbí “ìkùukùu.”

Tàbí “Ìkùukùu.”

Tàbí “àwọsánmà.”

Ní Héb., “àtíbàbà.”

Ní Héb., “ìmọ́lẹ̀.”

Ní Héb., “gbòǹgbò.”

Tàbí kó jẹ́, “gbèjà.”

Tàbí kó jẹ́, “ohun.”

Ní Héb., “fi èdìdì sí ọwọ́ gbogbo èèyàn.”

Tàbí “ìkùukùu.”

Tàbí “ìkùukùu.”

Tàbí “ilẹ̀ eléso ní ayé.”

Ní Héb., “ọ̀pá.”

Tàbí “pàṣẹ fún.”

Tàbí “ìkùukùu.”

Tàbí “ìkùukùu.”

Tàbí “ìkùukùu.”

Tàbí “rọ òfúrufú.”

Ìyẹn, ìmọ́lẹ̀ oòrùn.

Tàbí “àwọsánmà.”

Ní Héb., “tó gbọ́n ní ọkàn.”

Àkànlò èdè Hébérù tó ń tọ́ka sí àwọn áńgẹ́lì gẹ́gẹ́ bí ọmọ Ọlọ́run.

Ní Héb., “ilé ọlẹ̀.”

Ní Héb., “láwọn ọjọ́ rẹ.”

Tàbí “òjìji ikú.”

Ní Héb., “ọjọ́.”

Tàbí kó jẹ́, “mànàmáná.”

Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ àwọn ìràwọ̀ Píléádésì ní àgbájọ ìràwọ̀ Taurus.

Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ àgbájọ ìràwọ̀ Óríónì.

Ní Héb., “Másárótì.” Ní 2Ọb 23:5, ọ̀rọ̀ tó jọ èyí, tí wọ́n sì máa ń lò fún ohun tó bá pọ̀ ń tọ́ka sí àwọn àgbájọ ìràwọ̀ sódíákì.

Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ àgbájọ ìràwọ̀ Béárì Ńlá (ìyẹn, Ursa Major).

Tàbí kó jẹ́, “Rẹ̀.”

Tàbí kó jẹ́, “sínú èèyàn.”

Tàbí kó jẹ́, “fún ọkàn.”

Tàbí “àwọsánmà.”

Tàbí oríṣi kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ kan tí wọ́n ń pè ní onager.

Tàbí “ibùjẹ ẹran.”

Tàbí “fọ́ ilẹ̀.”

Ní Héb., “irúgbìn.”

Ní Héb., “mú kó gbàgbé.”

Tàbí “gọ̀gọ̀.”

Ní Héb., “Ó ń jáde lọ pàdé ìhámọ́ra.”

Ní Héb., “gbé ilẹ̀ (ayé) mì.”

Tàbí kó jẹ́, “Kì í gbà gbọ́.”

Ní Héb., “gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ àpáta.”

Tàbí “ìdájọ́ mi kò lẹ́sẹ̀ nílẹ̀ ni.”

Ní Héb., “De ojú wọn.”

Tàbí “yìn ọ́.”

Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ erinmi.

Ní Héb., “Òun ni ìbẹ̀rẹ̀.”

Iyẹn, koríko etí omi.

Ní Héb., “ìdẹkùn.”

Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ ọ̀nì.

Ní Héb., “ewéko etídò.”

Ní Héb., “ẹ̀gún.”

Ìyẹn, ọ̀kọ̀ tí wọ́n fi ń pa ẹja ńlá.

Tàbí “ṣe ni wàá ṣubú lulẹ̀.”

Ní Héb., “ojú.”

Tàbí kó jẹ́, “Ọ̀wọ́ àwọn ìpẹ́ rẹ̀ ló ń mú kó gbéra ga.”

Tàbí “yíhùn pa dà.”

Ní Héb., “Ó dájú pé màá gbé ojú rẹ̀ sókè.”

Ní Héb., “Jèhófà mú ìdè Jóòbù kúrò.”

Ní Héb., “Ó darúgbó, ó sì lọ́jọ́ lórí.”

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́