ÀKỌSÍLẸ̀ MÁTÍÙ
1 Ìwé ìtàn* nípa Jésù Kristi,* ọmọ Dáfídì,+ ọmọ Ábúráhámù:+
Ísákì bí Jékọ́bù;+
Jékọ́bù bí Júdà+ àti àwọn arákùnrin rẹ̀;
3 Támárì bí Pérésì àti Síírà+ fún Júdà;
Pérésì bí Hésírónì;+
Hésírónì bí Rámù;+
4 Rámù bí Ámínádábù;
Ámínádábù bí Náṣónì;+
Náṣónì bí Sálímọ́nì;
5 Ráhábù+ bí Bóásì fún Sálímọ́nì;
Rúùtù bí Óbédì fún Bóásì;+
Óbédì bí Jésè;+
Ìyàwó Ùráyà bí Sólómọ́nì+ fún Dáfídì;
Rèhóbóámù bí Ábíjà;
Ábíjà bí Ásà;+
Jèhóṣáfátì bí Jèhórámù;+
Jèhórámù bí Ùsáyà;
Jótámù bí Áhásì;+
Áhásì bí Hẹsikáyà;+
Mánásè bí Ámọ́nì;+
Ámọ́nì bí Jòsáyà;+
11 Jòsáyà+ bí Jekonáyà+ àti àwọn arákùnrin rẹ̀ nígbà tí wọ́n kó wọn lọ sí Bábílónì.+
12 Lẹ́yìn tí wọ́n kó wọn lọ sí Bábílónì, Jekonáyà bí Ṣéálítíẹ́lì;
Ṣéálítíẹ́lì bí Serubábélì;+
13 Serubábélì bí Ábíúdù;
Ábíúdù bí Élíákímù;
Élíákímù bí Ásórì;
14 Ásórì bí Sádókù;
Sádókù bí Ákímù;
Ákímù bí Élíúdù;
15 Élíúdù bí Élíásárì;
Élíásárì bí Mátáánì;
Mátáánì bí Jékọ́bù;
16 Jékọ́bù bí Jósẹ́fù ọkọ Màríà, ẹni tó bí Jésù,+ tí à ń pè ní Kristi.+
17 Torí náà, gbogbo ìran náà látọ̀dọ̀ Ábúráhámù dórí Dáfídì jẹ́ ìran mẹ́rìnlá (14); látọ̀dọ̀ Dáfídì di ìgbà tí wọ́n kó wọn lọ sí Bábílónì, ìran mẹ́rìnlá (14); látìgbà tí wọ́n kó wọn lọ sí Bábílónì di ìgbà Kristi, ìran mẹ́rìnlá (14).
18 Àmọ́ bí wọ́n ṣe bí Jésù Kristi nìyí. Nígbà tí Màríà ìyá rẹ̀ àti Jósẹ́fù ń fẹ́ra wọn sọ́nà, ó ṣẹlẹ̀ pé ó lóyún nípasẹ̀ ẹ̀mí mímọ́*+ kí wọ́n tó so wọ́n pọ̀. 19 Àmọ́ torí pé olódodo ni Jósẹ́fù ọkọ rẹ̀, tí kò sì fẹ́ dójú tì í ní gbangba, ó pinnu láti kọ̀ ọ́ sílẹ̀ ní bòókẹ́lẹ́.+ 20 Ṣùgbọ́n lẹ́yìn tó fara balẹ̀ ro ọ̀rọ̀ yìí, wò ó! áńgẹ́lì Jèhófà* fara hàn án lójú àlá, ó sọ pé: “Jósẹ́fù, ọmọ Dáfídì, má bẹ̀rù láti mú Màríà ìyàwó rẹ lọ sílé, torí oyún inú rẹ̀* jẹ́ nípasẹ̀ ẹ̀mí mímọ́.+ 21 Ó máa bí ọmọkùnrin kan, kí o pe orúkọ rẹ̀ ní Jésù,*+ torí ó máa gba àwọn èèyàn rẹ̀ kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ wọn.”+ 22 Gbogbo èyí ṣẹlẹ̀ kí ohun tí Jèhófà* sọ nípasẹ̀ wòlíì rẹ̀ lè ṣẹ, pé: 23 “Wò ó! Wúńdíá náà máa lóyún, ó sì máa bí ọmọkùnrin kan, wọ́n máa pe orúkọ rẹ̀ ní Ìmánúẹ́lì,”+ tó túmọ̀ sí, “Ọlọ́run Wà Pẹ̀lú Wa.”+
24 Jósẹ́fù wá jí lójú oorun, ó sì ṣe ohun tí áńgẹ́lì Jèhófà* ní kó ṣe, ó mú ìyàwó rẹ̀ lọ sílé. 25 Àmọ́ kò ní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú rẹ̀ títí ó fi bí ọmọkùnrin kan,+ ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní Jésù.+
2 Lẹ́yìn tí wọ́n bí Jésù ní Bẹ́tílẹ́hẹ́mù+ ti Jùdíà ní àwọn ọjọ́ Ọba Hẹ́rọ́dù,*+ wò ó! àwọn awòràwọ̀* wá sí Jerúsálẹ́mù láti Ìlà Oòrùn, 2 wọ́n sọ pé: “Ibo ni ọba àwọn Júù tí wọ́n bí wà?+ Torí a rí ìràwọ̀ rẹ̀ nígbà tí a wà ní Ìlà Oòrùn, a sì ti wá ká lè forí balẹ̀* fún un.” 3 Nígbà tí Ọba Hẹ́rọ́dù gbọ́ èyí, ọkàn rẹ̀ ò balẹ̀, òun àti gbogbo Jerúsálẹ́mù. 4 Ó kó gbogbo àwọn olórí àlùfáà àtàwọn akọ̀wé òfin àwọn èèyàn náà jọ, ó sì wádìí ibi tí wọ́n á ti bí Kristi* lọ́wọ́ wọn. 5 Wọ́n sọ fún un pé: “Bẹ́tílẹ́hẹ́mù+ ti Jùdíà ni, torí bí a ṣe kọ ọ́ nípasẹ̀ wòlíì nìyí: 6 ‘Ìwọ Bẹ́tílẹ́hẹ́mù ti ilẹ̀ Júdà, lọ́nàkọnà, ìwọ kọ́ ni ìlú tó rẹlẹ̀ jù lára àwọn gómìnà Júdà, torí inú rẹ ni alákòóso ti máa jáde wá, ẹni tó máa ṣe olùṣọ́ àgùntàn àwọn èèyàn mi Ísírẹ́lì.’”+
7 Hẹ́rọ́dù wá ránṣẹ́ pe àwọn awòràwọ̀ náà ní bòókẹ́lẹ́, ó sì fara balẹ̀ wádìí àkókò tí ìràwọ̀ náà fara hàn lọ́wọ́ wọn. 8 Nígbà tó ń rán wọn lọ sí Bẹ́tílẹ́hẹ́mù, ó sọ pé: “Ẹ lọ fara balẹ̀ wá ọmọ kékeré náà, tí ẹ bá sì ti rí i, ẹ pa dà wá jábọ̀ fún mi, kí èmi náà lè lọ forí balẹ̀ fún un.” 9 Lẹ́yìn tí wọ́n gbọ́ ohun tí ọba sọ, wọ́n lọ, sì wò ó! ìràwọ̀ tí wọ́n rí nígbà tí wọ́n wà ní Ìlà Oòrùn+ ń lọ níwájú wọn, títí ó fi dúró lókè ibi tí ọmọ kékeré náà wà. 10 Nígbà tí wọ́n rí ìràwọ̀ náà, inú wọn dùn gidigidi. 11 Nígbà tí wọ́n sì wọ ilé náà, wọ́n rí ọmọ kékeré náà pẹ̀lú Màríà ìyá rẹ̀, wọ́n wá wólẹ̀, wọ́n sì forí balẹ̀* fún un. Wọ́n tún ṣí àwọn ìṣúra wọn, wọ́n sì fún un lẹ́bùn, ìyẹn wúrà, oje igi tùràrí àti òjíá. 12 Àmọ́ torí pé wọ́n ti gba ìkìlọ̀ láti ọ̀run lójú àlá+ pé kí wọ́n má pa dà sọ́dọ̀ Hẹ́rọ́dù, wọ́n gba ọ̀nà míì lọ sí ilẹ̀ wọn.
13 Lẹ́yìn tí wọ́n lọ, wò ó! áńgẹ́lì Jèhófà* fara han Jósẹ́fù lójú àlá,+ ó sọ pé: “Dìde, mú ọmọ kékeré náà àti ìyá rẹ̀, kí o sì sá lọ sí Íjíbítì, kí o dúró síbẹ̀ títí màá fi bá ọ sọ̀rọ̀, torí Hẹ́rọ́dù ti fẹ́ máa wá ọmọ kékeré náà kiri kó lè pa á.” 14 Jósẹ́fù bá dìde, ó mú ọmọ kékeré náà àti ìyá rẹ̀ ní òru, ó sì lọ sí Íjíbítì. 15 Ó dúró síbẹ̀ títí Hẹ́rọ́dù fi kú. Èyí mú ohun tí Jèhófà* sọ nípasẹ̀ wòlíì rẹ̀ ṣẹ, pé: “Láti Íjíbítì ni mo ti pe ọmọkùnrin mi.”+
16 Nígbà tí Hẹ́rọ́dù rí i pé àwọn awòràwọ̀ náà ti já ọgbọ́n òun, inú bí i gidigidi, ó ránṣẹ́, ó sì ní kí wọ́n pa gbogbo ọmọkùnrin ní Bẹ́tílẹ́hẹ́mù àti ní gbogbo agbègbè rẹ̀, láti ọmọ ọdún méjì sí ìsàlẹ̀, gẹ́gẹ́ bí àkókò tó fara balẹ̀ wádìí lọ́wọ́ àwọn awòràwọ̀ náà.+ 17 Ohun tí a sọ nípasẹ̀ wòlíì Jeremáyà wá ṣẹ, pé: 18 “A gbọ́ ohùn kan ní Rámà, ẹkún àti ìpohùnréré ẹkún púpọ̀. Réṣẹ́lì+ ló ń sunkún torí àwọn ọmọ rẹ̀, kò sì fẹ́ kí wọ́n tu òun nínú, torí pé wọn kò sí mọ́.”+
19 Lẹ́yìn tí Hẹ́rọ́dù kú, wò ó! áńgẹ́lì Jèhófà* fara han Jósẹ́fù lójú àlá+ ní Íjíbítì, 20 ó sì sọ pé: “Dìde, mú ọmọ kékeré náà àti ìyá rẹ̀, kí o sì lọ sí ilẹ̀ Ísírẹ́lì, torí àwọn tó fẹ́ gba ẹ̀mí* ọmọ kékeré náà ti kú.” 21 Torí náà, ó dìde, ó mú ọmọ kékeré náà àti ìyá rẹ̀, ó sì lọ sí ilẹ̀ Ísírẹ́lì. 22 Àmọ́ nígbà tó gbọ́ pé Ákíláọ́sì ló ń ṣàkóso ní Jùdíà ní ipò Hẹ́rọ́dù bàbá rẹ̀, ẹ̀rù bà á láti lọ síbẹ̀. Yàtọ̀ síyẹn, torí a kìlọ̀ fún un láti ọ̀run lójú àlá,+ ó kúrò níbẹ̀ lọ sí ìpínlẹ̀ Gálílì.+ 23 Ó wá lọ ń gbé ní ìlú kan tí à ń pè ní Násárẹ́tì,+ kí ohun tí a sọ nípasẹ̀ àwọn wòlíì lè ṣẹ, pé: “A máa pè é ní ará Násárẹ́tì.”*+
3 Nígbà yẹn, Jòhánù+ Arinibọmi wá, ó ń wàásù+ ní aginjù Jùdíà, 2 ó ń sọ pé: “Ẹ ronú pìwà dà, torí Ìjọba ọ̀run ti sún mọ́lé.”+ 3 Òun gangan ni ẹni tí wòlíì Àìsáyà+ sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ pé: “Ohùn ẹnì kan ń ké nínú aginjù pé: ‘Ẹ ṣètò ọ̀nà Jèhófà!* Ẹ mú àwọn ọ̀nà rẹ̀ tọ́.’”+ 4 Jòhánù wọ aṣọ tí wọ́n fi irun ràkúnmí ṣe, ó sì de àmùrè tí wọ́n fi awọ ṣe mọ́ ìbàdí rẹ̀.+ Eéṣú àti oyin ìgàn ni oúnjẹ rẹ̀.+ 5 Àwọn èèyàn Jerúsálẹ́mù àti gbogbo Jùdíà àti gbogbo ìgbèríko tó yí Jọ́dánì ká máa ń lọ sọ́dọ̀ rẹ̀,+ 6 ó ń ṣèrìbọmi* fún wọn ní odò Jọ́dánì,+ wọ́n sì ń jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ wọn ní gbangba.
7 Nígbà tó rí i tí ọ̀pọ̀ lára àwọn Farisí àti Sadusí+ ń wá síbi ìrìbọmi náà, ó sọ fún wọn pé: “Ẹ̀yin ọmọ paramọ́lẹ̀,+ ta ló kìlọ̀ fún yín pé kí ẹ sá fún ìbínú tó ń bọ̀?+ 8 Torí náà, ẹ so èso tó yẹ ìrònúpìwàdà. 9 Ẹ má ṣe dá ara yín lójú, kí ẹ sì sọ fún ara yín pé, ‘A ní Ábúráhámù ní baba.’+ Torí mò ń sọ fún yín pé Ọlọ́run lè gbé àwọn ọmọ dìde fún Ábúráhámù látinú àwọn òkúta yìí. 10 Àáké ti wà níbi gbòǹgbò àwọn igi báyìí. Torí náà, gbogbo igi tí kò bá so èso tó dáa la máa gé lulẹ̀, tí a sì máa jù sínú iná.+ 11 Ní tèmi, mò ń fi omi batisí yín torí pé ẹ ronú pìwà dà,+ àmọ́ ẹni tó ń bọ̀ lẹ́yìn mi lágbára jù mí lọ, ẹni tí mi ò tó bọ́ bàtà rẹ̀.+ Ẹni yẹn máa fi ẹ̀mí mímọ́+ àti iná+ batisí yín. 12 Ṣọ́bìrì tó fi ń fẹ́ ọkà wà lọ́wọ́ rẹ̀, ó sì máa gbá ibi ìpakà rẹ̀ mọ́ tónítóní, ó máa kó àlìkámà* rẹ̀ jọ sínú ilé ìkẹ́rùsí, àmọ́ ó máa fi iná+ tí kò ṣeé pa sun ìyàngbò.”*
13 Lẹ́yìn náà, Jésù wá láti Gálílì sí Jọ́dánì, ó wá sọ́dọ̀ Jòhánù kó lè ṣèrìbọmi fún òun.+ 14 Àmọ́ ẹni yẹn gbìyànjú láti dá a dúró, ó sọ pé: “Ìwọ ló yẹ kí o ṣèrìbọmi fún mi, ṣé ọ̀dọ̀ mi lo wá ń bọ̀ ni?” 15 Jésù sọ fún un pé: “Jẹ́ kó rí bẹ́ẹ̀ lọ́tẹ̀ yìí, torí ọ̀nà yẹn ló yẹ ká gbà ṣe gbogbo ohun tó jẹ́ òdodo.” Kò wá dá a dúró mọ́. 16 Lẹ́yìn tí Jésù ṣèrìbọmi, ó jáde látinú omi lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀; sì wò ó! ọ̀run ṣí sílẹ̀,+ ó sì rí i tí ẹ̀mí Ọlọ́run ń sọ̀ kalẹ̀ bí àdàbà bọ̀ wá sórí rẹ̀.+ 17 Wò ó! Ohùn kan tún dún láti ọ̀run+ pé: “Èyí ni Ọmọ mi,+ àyànfẹ́, ẹni tí mo ti tẹ́wọ́ gbà.”+
4 Ẹ̀mí wá darí Jésù lọ sínú aginjù kí Èṣù+ lè dán an wò.+ 2 Lẹ́yìn tó ti gbààwẹ̀ fún ogójì (40) ọ̀sán àti ogójì (40) òru, ebi bẹ̀rẹ̀ sí í pa á. 3 Adánniwò náà+ wá bá a, ó sì sọ fún un pé: “Tí o bá jẹ́ ọmọ Ọlọ́run, sọ fún àwọn òkúta yìí pé kí wọ́n di búrẹ́dì.” 4 Àmọ́ ó dáhùn pé: “A ti kọ ọ́ pé: ‘Kì í ṣe oúnjẹ nìkan ṣoṣo ló ń mú kí èèyàn wà láàyè, àmọ́ gbogbo ọ̀rọ̀ tó ń ti ẹnu Jèhófà* jáde ni èèyàn fi ń wà láàyè.’”+
5 Lẹ́yìn náà, Èṣù mú un lọ sí ìlú mímọ́,+ ó mú un dúró lórí ògiri orí òrùlé* tẹ́ńpìlì,+ 6 ó sì sọ fún un pé: “Tí o bá jẹ́ ọmọ Ọlọ́run, bẹ́ sílẹ̀, torí a ti kọ ọ́ pé: ‘Ó máa pàṣẹ fún àwọn áńgẹ́lì rẹ̀ nítorí rẹ’ àti pé ‘Wọ́n á fi ọwọ́ wọn gbé ọ, kí o má bàa fi ẹsẹ̀ rẹ gbá òkúta.’”+ 7 Jésù sọ fún un pé: “A tún ti kọ ọ́ pé: ‘O ò gbọ́dọ̀ dán Jèhófà* Ọlọ́run rẹ wò.’”+
8 Èṣù tún mú un lọ sí òkè kan tó ga lọ́nà tó ṣàrà ọ̀tọ̀, ó sì fi gbogbo ìjọba ayé àti ògo wọn hàn án.+ 9 Ó sọ fún un pé: “Gbogbo nǹkan yìí ni màá fún ọ tí o bá wólẹ̀, tí o sì jọ́sìn mi lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo.” 10 Àmọ́, Jésù sọ fún un pé: “Kúrò lọ́dọ̀ mi, Sátánì! Torí a ti kọ ọ́ pé: ‘Jèhófà* Ọlọ́run rẹ ni o gbọ́dọ̀ jọ́sìn,+ òun nìkan ṣoṣo sì ni o gbọ́dọ̀ ṣe iṣẹ́ ìsìn mímọ́ fún.’”+ 11 Èṣù wá fi í sílẹ̀,+ sì wò ó! àwọn áńgẹ́lì wá, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe ìránṣẹ́ fún un.+
12 Nígbà tó gbọ́ pé wọ́n ti mú Jòhánù,+ ó fi ibẹ̀ sílẹ̀ lọ sí Gálílì.+ 13 Bákan náà, lẹ́yìn tó kúrò ní Násárẹ́tì, ó wá lọ ń gbé ní Kápánáúmù + lẹ́gbẹ̀ẹ́ òkun ní agbègbè Sébúlúnì àti Náfútálì, 14 kí ohun tí a sọ nípasẹ̀ wòlíì Àìsáyà lè ṣẹ, ẹni tó sọ pé: 15 “Ìwọ ilẹ̀ Sébúlúnì àti ilẹ̀ Náfútálì, ní ojú ọ̀nà òkun, ní òdìkejì Jọ́dánì, Gálílì àwọn orílẹ̀-èdè! 16 Àwọn èèyàn tó jókòó sínú òkùnkùn rí ìmọ́lẹ̀ tó mọ́lẹ̀ yòò, ní ti àwọn tó jókòó sí agbègbè òjìji ikú, ìmọ́lẹ̀+ tàn sórí wọn.”+ 17 Àtìgbà yẹn lọ ni Jésù ti bẹ̀rẹ̀ sí í wàásù, tó sì ń sọ pé: “Ẹ ronú pìwà dà, torí Ìjọba ọ̀run ti sún mọ́lé.”+
18 Bó ṣe ń rìn lọ létí Òkun Gálílì, ó rí àwọn méjì tí wọ́n jẹ́ tẹ̀gbọ́n-tàbúrò, Símónì tí wọ́n ń pè ní Pétérù+ àti Áńdérù arákùnrin rẹ̀, tí wọ́n ń ju àwọ̀n sínú òkun, torí apẹja ni wọ́n.+ 19 Ó sọ fún wọn pé: “Ẹ máa tẹ̀ lé mi, màá sì sọ yín di apẹja èèyàn.”+ 20 Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, wọ́n pa àwọ̀n wọn tì, wọ́n sì tẹ̀ lé e.+ 21 Nígbà tó kúrò níbẹ̀, ó rí àwọn méjì míì tí wọ́n jẹ́ tẹ̀gbọ́n-tàbúrò, Jémíìsì ọmọ Sébédè àti Jòhánù arákùnrin rẹ̀.+ Inú ọkọ̀ ojú omi ni wọ́n wà pẹ̀lú Sébédè bàbá wọn, wọ́n ń tún àwọ̀n wọn ṣe, ó sì pè wọ́n.+ 22 Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, wọ́n fi ọkọ̀ ojú omi náà àti bàbá wọn sílẹ̀, wọ́n sì tẹ̀ lé e.
23 Ó lọ káàkiri gbogbo Gálílì,+ ó ń kọ́ni nínú àwọn sínágọ́gù wọn,+ ó sì ń wàásù ìhìn rere Ìjọba náà, ó ń wo onírúurú àìsàn àti onírúurú àìlera sàn láàárín àwọn èèyàn.+ 24 Òkìkí rẹ̀ kàn ká gbogbo Síríà, wọ́n sì gbé gbogbo àwọn tí onírúurú àìsàn ń ṣe, tí wọ́n sì ń joró wá sọ́dọ̀ rẹ̀,+ pẹ̀lú àwọn tí ẹ̀mí èṣù ń yọ lẹ́nu,+ àwọn tó ní wárápá + àti àrùn rọpárọsẹ̀, ó sì wò wọ́n sàn. 25 Torí náà, ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn tẹ̀ lé e láti Gálílì, Dekapólì,* Jerúsálẹ́mù, Jùdíà àti láti òdìkejì Jọ́dánì.
5 Nígbà tó rí ọ̀pọ̀ èèyàn, ó lọ sórí òkè; lẹ́yìn tó jókòó, àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ wá sọ́dọ̀ rẹ̀. 2 Ó wá la ẹnu rẹ̀, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ wọn, ó sọ pé:
3 “Aláyọ̀ ni àwọn tó ń wá ìtọ́sọ́nà Ọlọ́run,*+ torí Ìjọba ọ̀run jẹ́ tiwọn.
4 “Aláyọ̀ ni àwọn tó ń ṣọ̀fọ̀, torí a máa tù wọ́n nínú.+
5 “Aláyọ̀ ni àwọn oníwà tútù,*+ torí wọ́n máa jogún ayé.+
6 “Aláyọ̀ ni àwọn tí ebi òdodo ń pa,+ tí òùngbẹ òdodo sì ń gbẹ, torí wọ́n máa yó.*+
7 “Aláyọ̀ ni àwọn aláàánú,+ torí a máa ṣàánú wọn.
8 “Aláyọ̀ ni àwọn tí ọkàn wọn mọ́,+ torí wọ́n máa rí Ọlọ́run.
9 “Aláyọ̀ ni àwọn tó ń wá àlàáfíà,*+ torí a máa pè wọ́n ní ọmọ Ọlọ́run.
10 “Aláyọ̀ ni àwọn tí wọ́n ṣe inúnibíni sí nítorí òdodo,+ torí Ìjọba ọ̀run jẹ́ tiwọn.
11 “Aláyọ̀ ni yín tí àwọn èèyàn bá pẹ̀gàn yín,+ tí wọ́n ṣe inúnibíni sí yín,+ tí wọ́n sì parọ́ oríṣiríṣi ohun burúkú mọ́ yín nítorí mi.+ 12 Ẹ máa yọ̀, kí inú yín sì dùn gidigidi,+ torí èrè yín+ pọ̀ ní ọ̀run, torí bí wọ́n ṣe ṣe inúnibíni sí àwọn wòlíì tó wà ṣáájú yín nìyẹn.+
13 “Ẹ̀yin ni iyọ̀+ ayé, àmọ́ tí iyọ̀ ò bá lágbára mọ́, báwo ló ṣe máa pa dà ní adùn rẹ̀? Kò ṣeé lò fún ohunkóhun mọ́, àfi ká dà á síta,+ kí àwọn èèyàn tẹ̀ ẹ́ mọ́lẹ̀.
14 “Ẹ̀yin ni ìmọ́lẹ̀ ayé.+ Ìlú tó bá wà lórí òkè ò lè fara sin. 15 Tí àwọn èèyàn bá tan fìtílà, wọn kì í gbé e sábẹ́ apẹ̀rẹ̀,* orí ọ̀pá fìtílà ni wọ́n ń gbé e sí, á sì tàn sára gbogbo àwọn tó wà nínú ilé.+ 16 Bákan náà, ẹ jẹ́ kí ìmọ́lẹ̀ yín máa tàn níwájú àwọn èèyàn,+ kí wọ́n lè rí àwọn iṣẹ́ rere yín,+ kí wọ́n sì fògo fún Baba yín tó wà ní ọ̀run.+
17 “Ẹ má rò pé mo wá láti pa Òfin tàbí àwọn Wòlíì run. Mi ò wá láti pa á run, àmọ́ láti mú un ṣẹ.+ 18 Lóòótọ́ ni mo sọ fún yín pé, tí ọ̀run àti ayé bá tiẹ̀ yára kọjá lọ, lẹ́tà tó kéré jù tàbí ìlà kan lára lẹ́tà kò ní kúrò nínú Òfin títí gbogbo nǹkan fi máa ṣẹlẹ̀.+ 19 Torí náà, ẹnikẹ́ni tó bá tẹ ọ̀kan nínú àwọn àṣẹ tó kéré jù yìí lójú, tó sì ń kọ́ àwọn míì pé kí wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀, a máa pè é ní ẹni tó kéré jù lọ ní ìsopọ̀ pẹ̀lú Ìjọba ọ̀run. Àmọ́ ẹnikẹ́ni tó bá ń pa á mọ́, tó sì ń fi kọ́ni, a máa pè é ní ẹni ńlá ní ìsopọ̀ pẹ̀lú Ìjọba ọ̀run. 20 Torí mò ń sọ fún yín pé tí òdodo yín ò bá ju ti àwọn akọ̀wé òfin àti àwọn Farisí lọ,+ ó dájú pé ẹ ò ní wọ Ìjọba ọ̀run.+
21 “Ẹ gbọ́ pé a sọ fún àwọn èèyàn àtijọ́ pé: ‘O ò gbọ́dọ̀ pààyàn,+ àmọ́ ẹnikẹ́ni tó bá pààyàn máa jíhìn fún ilé ẹjọ́.’+ 22 Àmọ́ mò ń sọ fún yín pé gbogbo ẹni tí kò bá yéé bínú+ sí arákùnrin rẹ̀ máa jíhìn fún ilé ẹjọ́; ẹnikẹ́ni tó bá sì sọ̀rọ̀ àbùkù tí kò ṣeé gbọ́ sétí sí arákùnrin rẹ̀ máa jíhìn fún Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ; àmọ́ ẹnikẹ́ni tó bá sọ pé, ‘Ìwọ òpònú aláìníláárí!’ Gẹ̀hẹ́nà* oníná ló máa tọ́ sí i.+
23 “Tí o bá ń mú ẹ̀bùn rẹ bọ̀ níbi pẹpẹ,+ tí o sì rántí níbẹ̀ pé arákùnrin rẹ ní ohun kan lòdì sí ọ, 24 fi ẹ̀bùn rẹ sílẹ̀ níbẹ̀ níwájú pẹpẹ, kí o sì lọ. Kọ́kọ́ wá àlàáfíà pẹ̀lú arákùnrin rẹ, lẹ́yìn náà, kí o pa dà wá fi ẹ̀bùn rẹ rúbọ.+
25 “Tètè yanjú ọ̀rọ̀ pẹ̀lú ẹni tó fẹ̀sùn kàn ọ́ lábẹ́ òfin, nígbà tí o wà pẹ̀lú rẹ̀ lójú ọ̀nà ibẹ̀, kí ẹni tó fẹ̀sùn kàn ọ́ má bàa fi ọ́ lé adájọ́ lọ́wọ́ lọ́nà kan ṣáá, kí adájọ́ sì fi ọ́ lé òṣìṣẹ́ ilé ẹjọ́ lọ́wọ́, kí wọ́n sì fi ọ́ sẹ́wọ̀n.+ 26 Lóòótọ́ ni mo sọ fún ọ pé, ó dájú pé o ò ní kúrò níbẹ̀ títí wàá fi san ẹyọ owó kékeré tó kù* tí o jẹ.
27 “Ẹ gbọ́ pé a sọ pé: ‘O ò gbọ́dọ̀ ṣe àgbèrè.’+ 28 Àmọ́ mò ń sọ fún yín pé ẹnikẹ́ni tó bá tẹjú mọ́ obìnrin+ kan lọ́nà tí á fi wù ú láti bá a ṣe ìṣekúṣe, ó ti bá a ṣe àgbèrè nínú ọkàn rẹ̀.+ 29 Tí ojú ọ̀tún rẹ bá ń mú ọ kọsẹ̀, yọ ọ́, kí o sì sọ ọ́ nù kúrò lọ́dọ̀ rẹ.+ Torí ó sàn kí o má ní ẹ̀yà ara kan ju kí a ju gbogbo ara rẹ sínú Gẹ̀hẹ́nà.*+ 30 Bákan náà, tí ọwọ́ ọ̀tún rẹ bá ń mú ọ kọsẹ̀, gé e, kí o sì sọ ọ́ nù kúrò lọ́dọ̀ rẹ.+ Torí ó sàn kí o má ní ẹ̀yà ara kan ju kí o bá gbogbo ara rẹ nínú Gẹ̀hẹ́nà.*+
31 “A tún sọ pé: ‘Ẹnikẹ́ni tó bá kọ ìyàwó rẹ̀ sílẹ̀, kó fún un ní ìwé ẹ̀rí ìkọ̀sílẹ̀.’+ 32 Àmọ́ mò ń sọ fún yín pé gbogbo ẹni tó bá kọ ìyàwó rẹ̀ sílẹ̀, tí kò bá jẹ́ torí ìṣekúṣe,* lè mú kí obìnrin náà ṣe àgbèrè, ẹnikẹ́ni tó bá sì fẹ́ obìnrin tí wọ́n ti kọ̀ sílẹ̀ ti ṣe àgbèrè.+
33 “Ẹ tún gbọ́ pé a sọ fún àwọn èèyàn àtijọ́ pé: ‘O ò gbọ́dọ̀ búra láìṣe é,+ àmọ́ o gbọ́dọ̀ san àwọn ẹ̀jẹ́ rẹ fún Jèhófà.’*+ 34 Àmọ́ mò ń sọ fún yín pé: Má ṣe búra rárá,+ ì báà jẹ́ ọ̀run lo fi búra, torí ìtẹ́ Ọlọ́run ni; 35 tàbí ayé, torí àpótí ìtìsẹ̀ rẹ̀ ni;+ tàbí Jerúsálẹ́mù, torí ìlú Ọba ńlá náà ni.+ 36 O ò gbọ́dọ̀ fi orí rẹ búra, torí o ò lè sọ irun kan di funfun tàbí dúdú. 37 Ẹ ṣáà ti jẹ́ kí ọ̀rọ̀ yín, ‘Bẹ́ẹ̀ ni’ jẹ́ bẹ́ẹ̀ ni, kí ‘Bẹ́ẹ̀ kọ́’ yín jẹ́ bẹ́ẹ̀ kọ́,+ torí ọ̀dọ̀ ẹni burúkú náà ni ohun tó bá ju èyí lọ ti wá.+
38 “Ẹ gbọ́ pé a sọ pé: ‘Ojú dípò ojú àti eyín dípò eyín.’+ 39 Àmọ́ mò ń sọ fún yín pé: Ẹ má ṣe ta ko ẹni burúkú, àmọ́ ẹnikẹ́ni tó bá gbá yín ní etí* ọ̀tún, ẹ yí èkejì sí i.+ 40 Tí ẹnì kan bá fẹ́ mú ọ lọ sí ilé ẹjọ́, kó sì gba aṣọ àwọ̀tẹ́lẹ̀ rẹ, jẹ́ kó gba aṣọ àwọ̀lékè rẹ pẹ̀lú;+ 41 tí ẹnì kan tó wà nípò àṣẹ bá sì fipá mú ọ láti ṣiṣẹ́ dé máìlì* kan, bá a dé máìlì méjì. 42 Tí ẹnì kan bá ń béèrè nǹkan lọ́wọ́ rẹ, fún un, má sì yíjú kúrò lọ́dọ̀ ẹni tó fẹ́ yá nǹkan* lọ́wọ́ rẹ.+
43 “Ẹ gbọ́ pé a sọ pé: ‘Kí o nífẹ̀ẹ́ ọmọnìkejì rẹ,+ kí o sì kórìíra ọ̀tá rẹ.’ 44 Àmọ́ mò ń sọ fún yín pé: Ẹ máa nífẹ̀ẹ́ àwọn ọ̀tá yín,+ kí ẹ sì máa gbàdúrà fún àwọn tó ń ṣe inúnibíni sí yín,+ 45 kí ẹ lè fi hàn pé ọmọ Baba yín tó wà ní ọ̀run lẹ jẹ́,+ torí ó ń mú kí oòrùn rẹ̀ ràn sórí àwọn èèyàn burúkú àtàwọn èèyàn rere, ó sì ń mú kí òjò rọ̀ sórí àwọn olódodo àti aláìṣòdodo.+ 46 Torí tí ẹ bá nífẹ̀ẹ́ àwọn tó nífẹ̀ẹ́ yín, kí ni èrè yín?+ Ṣebí ohun tí àwọn agbowó orí ń ṣe náà nìyẹn? 47 Tí ẹ bá sì ń kí àwọn arákùnrin yín nìkan, ohun àrà ọ̀tọ̀ wo lẹ̀ ń ṣe? Ṣebí ohun tí àwọn èèyàn orílẹ̀-èdè ń ṣe náà nìyẹn? 48 Kí ẹ jẹ́ pípé gẹ́lẹ́,* bí Baba yín ọ̀run ṣe jẹ́ pípé.+
6 “Kí ẹ rí i pé ẹ ò ṣe òdodo yín níwájú àwọn èèyàn, torí kí wọ́n lè rí yín;+ àìjẹ́ bẹ́ẹ̀, ẹ ò ní rí èrè kankan lọ́dọ̀ Baba yín tó wà ní ọ̀run. 2 Torí náà, tí o bá ń ṣe ìtọrẹ àánú,* má ṣe fun kàkàkí ṣáájú ara rẹ, bí àwọn alágàbàgebè ṣe ń ṣe nínú àwọn sínágọ́gù àti láwọn ojú ọ̀nà, kí àwọn èèyàn lè kan sáárá sí wọn. Lóòótọ́ ni mo sọ fún yín, wọ́n ti gba èrè wọn ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́. 3 Àmọ́ tí ìwọ bá ń ṣe ìtọrẹ àánú, má ṣe jẹ́ kí ọwọ́ òsì rẹ mọ ohun tí ọwọ́ ọ̀tún rẹ ń ṣe, 4 kí ìtọrẹ àánú tí o ṣe lè wà ní ìkọ̀kọ̀. Baba rẹ tó ń ríran ní ìkọ̀kọ̀ sì máa san ọ́ lẹ́san.+
5 “Bákan náà, tí ẹ bá ń gbàdúrà, ẹ má ṣe bíi ti àwọn alágàbàgebè,+ torí tí wọ́n bá ń gbàdúrà, wọ́n máa ń fẹ́ dúró nínú àwọn sínágọ́gù àti ní ìkóríta àwọn ọ̀nà tó bọ́ sí gbangba, kí àwọn èèyàn lè rí wọn.+ Lóòótọ́ ni mo sọ fún yín, wọ́n ti gba èrè wọn ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́. 6 Àmọ́ tí o bá ń gbàdúrà, lọ sínú yàrá àdáni rẹ, lẹ́yìn tí o bá ti ilẹ̀kùn rẹ, gbàdúrà sí Baba rẹ tó wà ní ìkọ̀kọ̀.+ Baba rẹ tó ń rí ohun tó wà ní ìkọ̀kọ̀ sì máa san ọ́ lẹ́san. 7 Tí o bá ń gbàdúrà, má sọ ohun kan náà ní àsọtúnsọ, bí àwọn èèyàn orílẹ̀-èdè ṣe máa ń ṣe, torí wọ́n rò pé àdúrà àwọn máa gbà torí bí wọ́n ṣe ń lo ọ̀rọ̀ púpọ̀. 8 Torí náà, ẹ má ṣe bíi tiwọn, torí Baba yín mọ àwọn ohun tí ẹ nílò,+ kódà kí ẹ tó béèrè lọ́wọ́ rẹ̀.
9 “Torí náà, ẹ máa gbàdúrà lọ́nà yìí:+
“‘Baba wa tí ń bẹ ní ọ̀run, kí orúkọ+ rẹ di mímọ́.*+ 10 Kí Ìjọba rẹ dé.+ Kí ìfẹ́ rẹ+ ṣẹ ní ayé,+ bíi ti ọ̀run. 11 Fún wa ní oúnjẹ òòjọ́ wa lónìí;+ 12 kí o sì dárí àwọn gbèsè wa jì wá, bí àwa náà ṣe dárí ji àwọn tó jẹ wá ní gbèsè.+ 13 Má sì mú wa wá sínú ìdẹwò,+ ṣùgbọ́n gbà wá* lọ́wọ́ ẹni burúkú náà.’+
14 “Torí tí ẹ bá dárí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn èèyàn jì wọ́n, Baba yín ọ̀run náà máa dárí jì yín;+ 15 àmọ́ tí ẹ kò bá dárí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn èèyàn jì wọ́n, Baba yín ò ní dárí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ yín jì yín.+
16 “Tí ẹ bá ń gbààwẹ̀,+ ẹ má fajú ro mọ́ bíi ti àwọn alágàbàgebè, torí wọ́n máa ń bojú jẹ́* kí àwọn èèyàn lè rí i pé wọ́n ń gbààwẹ̀.+ Lóòótọ́ ni mo sọ fún yín, wọ́n ti gba èrè wọn ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́. 17 Àmọ́ tí ìwọ bá ń gbààwẹ̀, fi òróró pa orí rẹ, kí o sì bọ́jú rẹ, 18 kó má bàa hàn sí àwọn èèyàn pé ò ń gbààwẹ̀, Baba rẹ tó wà ní ìkọ̀kọ̀ nìkan ni kó hàn sí. Baba rẹ tó ń rí ohun tó wà ní ìkọ̀kọ̀ sì máa san ọ́ lẹ́san.
19 “Ẹ má to ìṣúra pa mọ́ fún ara yín ní ayé mọ́,+ níbi tí òólá* ti ń jẹ nǹkan run, tí nǹkan ti ń dípẹtà, tí àwọn olè ń fọ́lé, tí wọ́n sì ń jalè. 20 Kàkà bẹ́ẹ̀, ẹ to ìṣúra pa mọ́ fún ara yín ní ọ̀run,+ níbi tí òólá kò ti lè jẹ nǹkan run, tí nǹkan ò ti lè dípẹtà,+ tí àwọn olè kò ti lè fọ́lé, kí wọ́n sì jalè. 21 Torí ibi tí ìṣúra yín bá wà, ibẹ̀ ni ọkàn yín náà máa wà.
22 “Ojú ni fìtílà ara.+ Tí ojú rẹ bá mú ọ̀nà kan,* gbogbo ara rẹ máa mọ́lẹ̀ yòò.* 23 Àmọ́ tí ojú rẹ bá ń ṣe ìlara,*+ gbogbo ara rẹ máa ṣókùnkùn. Tó bá jẹ́ òkùnkùn ni ìmọ́lẹ̀ tó wà nínú rẹ lóòótọ́, òkùnkùn yẹn mà pọ̀ o!
24 “Kò sí ẹni tó lè sin ọ̀gá méjì; àfi kó kórìíra ọ̀kan, kó sì nífẹ̀ẹ́ ìkejì+ tàbí kó fara mọ́ ọ̀kan, kó má sì ka ìkejì sí. Ẹ ò lè sin Ọlọ́run àti Ọrọ̀.+
25 “Torí náà, mo sọ fún yín pé: Ẹ yéé ṣàníyàn+ nípa ẹ̀mí* yín, ní ti ohun tí ẹ máa jẹ tàbí tí ẹ máa mu tàbí nípa ara yín, ní ti ohun tí ẹ máa wọ̀.+ Ṣé ẹ̀mí* ò ṣe pàtàkì ju oúnjẹ lọ ni, tí ara sì ṣe pàtàkì ju aṣọ lọ?+ 26 Ẹ fara balẹ̀ kíyè sí àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run;+ wọn kì í fúnrúgbìn tàbí kárúgbìn tàbí kí wọ́n kó nǹkan jọ sínú ilé ìkẹ́rùsí, síbẹ̀ Baba yín ọ̀run ń bọ́ wọn. Ṣé ẹ ò wá níye lórí jù wọ́n lọ ni? 27 Èwo nínú yín ló lè fi ìgbọ̀nwọ́* kan kún ìwàláàyè rẹ̀, tó bá ń ṣàníyàn?+ 28 Bákan náà, kí ló dé tí ẹ̀ ń ṣàníyàn nípa ohun tí ẹ máa wọ̀? Ẹ kẹ́kọ̀ọ́ lára àwọn òdòdó lílì inú pápá, bí wọ́n ṣe ń dàgbà; wọn kì í ṣe làálàá, wọn kì í sì í rànwú;* 29 àmọ́ mò ń sọ fún yín pé, a ò ṣe Sólómọ́nì+ pàápàá lọ́ṣọ̀ọ́ nínú gbogbo ògo rẹ̀ bí ọ̀kan lára àwọn yìí. 30 Tó bá jẹ́ pé báyìí ni Ọlọ́run ṣe ń wọ ewéko pápá láṣọ, tó wà lónìí, tí a sì sọ sínú ààrò lọ́la, ṣé kò wá ní wọ̀ yín láṣọ jù bẹ́ẹ̀ lọ, ẹ̀yin tí ìgbàgbọ́ yín kéré? 31 Torí náà, ẹ má ṣàníyàn láé,+ kí ẹ wá sọ pé, ‘Kí la máa jẹ?’ tàbí, ‘Kí la máa mu?’ tàbí, ‘Kí la máa wọ̀?’+ 32 Torí gbogbo nǹkan yìí ni àwọn orílẹ̀-èdè ń wá lójú méjèèjì. Baba yín ọ̀run mọ̀ pé ẹ nílò gbogbo nǹkan yìí.
33 “Torí náà, ẹ máa wá Ìjọba náà àti òdodo Rẹ̀ lákọ̀ọ́kọ́, gbogbo nǹkan mìíràn yìí la sì máa fi kún un fún yín.+ 34 Torí náà, ẹ má ṣàníyàn láé nípa ọ̀la,+ torí ọ̀la máa ní àwọn àníyàn tirẹ̀. Wàhálà ọjọ́ kọ̀ọ̀kan ti tó fún un.
7 “Ẹ yéé dáni lẹ́jọ́,+ kí a má bàa dá yín lẹ́jọ́; 2 torí bí ẹ bá ṣe dáni lẹ́jọ́ la ṣe máa dá yín lẹ́jọ́,+ òṣùwọ̀n tí ẹ sì fi ń díwọ̀n fúnni la máa fi díwọ̀n fún yín.+ 3 Kí ló wá dé tí ò ń wo pòròpórò tó wà nínú ojú arákùnrin rẹ, àmọ́ tí o ò kíyè sí igi ìrólé tó wà nínú ojú tìrẹ?+ 4 Àbí báwo lo ṣe lè sọ fún arákùnrin rẹ pé, ‘Jẹ́ kí n bá ọ yọ pòròpórò kúrò nínú ojú rẹ,’ nígbà tó jẹ́ pé, wò ó! igi ìrólé wà nínú ojú ìwọ fúnra rẹ? 5 Alágàbàgebè! Kọ́kọ́ yọ igi ìrólé kúrò nínú ojú tìrẹ, ìgbà yẹn lo máa wá ríran kedere láti yọ pòròpórò kúrò nínú ojú arákùnrin rẹ.
6 “Ẹ má ṣe fún àwọn ajá ní ohun tó jẹ́ mímọ́, ẹ má sì sọ àwọn péálì yín síwájú àwọn ẹlẹ́dẹ̀,+ kí wọ́n má bàa fi ẹsẹ̀ wọn tẹ̀ ẹ́ mọ́lẹ̀, kí wọ́n wá yíjú pa dà, kí wọ́n sì fà yín ya.
7 “Ẹ máa béèrè, a sì máa fún yín;+ ẹ máa wá kiri, ẹ sì máa rí; ẹ máa kan ilẹ̀kùn, a sì máa ṣí i fún yín;+ 8 torí gbogbo ẹni tó bá ń béèrè máa rí gbà,+ gbogbo ẹni tó bá ń wá kiri máa rí, gbogbo ẹni tó bá sì ń kan ilẹ̀kùn la máa ṣí i fún. 9 Ní tòótọ́, èwo nínú yín ló jẹ́ pé, tí ọmọ rẹ̀ bá béèrè búrẹ́dì, ó máa fún un ní òkúta? 10 Tó bá sì béèrè ẹja, kò ní fún un ní ejò, àbí ó máa fún un? 11 Torí náà, tí ẹ̀yin bá mọ bí ẹ ṣe ń fún àwọn ọmọ yín ní ẹ̀bùn tó dáa, bó tiẹ̀ jẹ́ pé ẹni burúkú ni yín, mélòómélòó wá ni Baba yín tó wà ní ọ̀run, ohun tó dáa+ ló máa fún àwọn tó ń béèrè lọ́wọ́ rẹ̀!+
12 “Torí náà, gbogbo ohun tí ẹ bá fẹ́ kí àwọn èèyàn ṣe sí yín ni kí ẹ̀yin náà máa ṣe sí wọn.+ Ní tòótọ́, ohun tí Òfin àti àwọn Wòlíì túmọ̀ sí nìyí.+
13 “Ẹ gba ẹnubodè tóóró wọlé,+ torí ẹnubodè tó lọ sí ìparun fẹ̀, ọ̀nà ibẹ̀ gbòòrò, àwọn tó ń gba ibẹ̀ wọlé sì pọ̀; 14 nígbà tó jẹ́ pé, ẹnubodè tó lọ sí ìyè rí tóóró, ọ̀nà ibẹ̀ há, àwọn díẹ̀ ló sì ń rí i.+
15 “Ẹ máa ṣọ́ra fún àwọn wòlíì èké+ tó ń wá sọ́dọ̀ yín nínú àwọ̀ àgùntàn,+ àmọ́ tó jẹ́ pé ọ̀yánnú ìkookò ni wọ́n ní inú.+ 16 Àwọn èso wọn lẹ máa fi dá wọn mọ̀. Àwọn èèyàn kì í kó èso àjàrà jọ láti ara ẹ̀gún, wọn kì í sì í kó ọ̀pọ̀tọ́ jọ láti ara òṣùṣú, àbí wọ́n máa ń ṣe bẹ́ẹ̀?+ 17 Bákan náà, gbogbo igi rere máa ń so èso rere, àmọ́ gbogbo igi tó ti jẹrà máa ń so èso tí kò ní láárí.+ 18 Igi rere ò lè so èso tí kò ní láárí, igi tó ti jẹrà ò sì lè so èso rere.+ 19 Gbogbo igi tí kò bá so èso rere la máa gé lulẹ̀, tí a sì máa jù sínú iná.+ 20 Torí náà, ní tòótọ́, èso àwọn èèyàn yẹn lẹ máa fi dá wọn mọ̀.+
21 “Kì í ṣe gbogbo ẹni tó ń pè mí ní, ‘Olúwa, Olúwa,’ ló máa wọ Ìjọba ọ̀run, àmọ́ ẹni tó ń ṣe ìfẹ́ Baba mi tó wà ní ọ̀run nìkan ló máa wọ̀ ọ́.+ 22 Ọ̀pọ̀ máa sọ fún mi ní ọjọ́ yẹn pé: ‘Olúwa, Olúwa,+ ṣebí a fi orúkọ rẹ sọ tẹ́lẹ̀, a fi orúkọ rẹ lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde, a sì fi orúkọ rẹ ṣe ọ̀pọ̀ iṣẹ́ agbára?’+ 23 Àmọ́, màá sọ fún wọn pé: ‘Mi ò mọ̀ yín rí! Ẹ kúrò lọ́dọ̀ mi, ẹ̀yin arúfin!’+
24 “Torí náà, gbogbo ẹni tó gbọ́ ọ̀rọ̀ mi yìí, tó sì ṣe é máa dà bí ọkùnrin kan tó ní òye, tó kọ́ ilé rẹ̀ sórí àpáta.+ 25 Òjò sì rọ̀, omi kún àkúnya, ìjì sì fẹ́ lu ilé náà, àmọ́ kò wó, torí pé orí àpáta ni ìpìlẹ̀ rẹ̀ wà. 26 Bákan náà, gbogbo ẹni tó gbọ́ ọ̀rọ̀ mi yìí, tí kò sì ṣe é máa dà bí òmùgọ̀ ọkùnrin tó kọ́ ilé rẹ̀ sórí iyanrìn.+ 27 Òjò sì rọ̀, omi kún àkúnya, ìjì sì fẹ́ lu ilé náà,+ àmọ́ kò lè dúró, ńṣe ló wó lulẹ̀ bẹẹrẹbẹ.”
28 Nígbà tí Jésù sọ àwọn ọ̀rọ̀ yìí tán, ohun tó ṣẹlẹ̀ ni pé bó ṣe ń kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ ya àwọn èrò náà lẹ́nu,+ 29 torí ṣe ló ń kọ́ wọn bí ẹni tó ní àṣẹ,+ kò kọ́ wọn bí àwọn akọ̀wé òfin wọn.
8 Lẹ́yìn tó sọ̀ kalẹ̀ látorí òkè náà, èrò rẹpẹtẹ rọ́ tẹ̀ lé e. 2 Wò ó! adẹ́tẹ̀ kan wá, ó sì forí balẹ̀* fún un, ó sọ pé: “Olúwa, tí o bá ṣáà ti fẹ́, o lè jẹ́ kí n mọ́.”+ 3 Torí náà, ó na ọwọ́ rẹ̀, ó sì fọwọ́ kàn án, ó ní: “Mo fẹ́ bẹ́ẹ̀! Kí o mọ́.”+ Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, a wẹ ẹ̀tẹ̀ rẹ̀ mọ́.+ 4 Jésù wá sọ fún un pé: “Rí i pé o ò sọ fún ẹnì kankan,+ àmọ́ lọ, kí o fi ara rẹ han àlùfáà,+ kí o sì mú ẹ̀bùn tí Mósè sọ lọ,+ kó lè jẹ́ ẹ̀rí fún wọn.”
5 Nígbà tó wọ Kápánáúmù, ọ̀gágun kan wá bá a, ó ń bẹ̀ ẹ́,+ 6 ó sì ń sọ pé: “Ọ̀gá, àrùn rọpárọsẹ̀ dá ìránṣẹ́ mi dùbúlẹ̀ sínú ilé, ìyà sì ń jẹ ẹ́ gidigidi.” 7 Ó sọ fún un pé: “Tí mo bá débẹ̀, màá wò ó sàn.” 8 Ọ̀gágun náà fèsì pé: “Ọ̀gá, mi ò yẹ lẹ́ni tí o lè wá sábẹ́ òrùlé rẹ̀, àmọ́ ṣáà ti sọ̀rọ̀, ara ìránṣẹ́ mi á sì yá. 9 Torí èmi náà wà lábẹ́ àṣẹ, mo sì ní àwọn ọmọ ogun tó wà lábẹ́ àṣẹ mi, tí mo bá sọ fún eléyìí pé, ‘Lọ!’ á lọ, tí mo bá sọ fún ẹlòmíì pé, ‘Wá!’ á wá, tí mo bá sì sọ fún ẹrú mi pé, ‘Ṣe báyìí!’ á ṣe é.” 10 Nígbà tí Jésù gbọ́ ohun tó sọ, ó yà á lẹ́nu, ó sì sọ fún àwọn tó ń tẹ̀ lé e pé: “Kí n sọ òótọ́ fún yín, mi ò tíì rí ẹnì kankan ní Ísírẹ́lì tó ní ìgbàgbọ́ tó lágbára tó báyìí.+ 11 Àmọ́ mo sọ fún yín pé ọ̀pọ̀ èèyàn láti ìlà oòrùn àti ìwọ̀ oòrùn máa wá, wọ́n á sì jókòó* sídìí tábìlì pẹ̀lú Ábúráhámù, Ísákì àti Jékọ́bù nínú Ìjọba ọ̀run;+ 12 àmọ́ a máa ju àwọn ọmọ Ìjọba náà sínú òkùnkùn níta. Ibẹ̀ ni wọ́n á ti máa sunkún, tí wọ́n á sì ti máa payín keke.”+ 13 Jésù wá sọ fún ọ̀gágun náà pé: “Máa lọ. Bí o ṣe fi hàn pé o nígbàgbọ́, kó rí bẹ́ẹ̀ fún ọ.”+ Ara ìránṣẹ́ náà sì yá ní wákàtí yẹn.+
14 Nígbà tí Jésù wọ ilé Pétérù, ó rí ìyá ìyàwó rẹ̀+ tí àìsàn ibà dá dùbúlẹ̀.+ 15 Ó sì fọwọ́ kan ọwọ́ obìnrin náà,+ ibà náà sì lọ, obìnrin náà wá dìde, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe ìránṣẹ́ fún un. 16 Àmọ́ nígbà tó di ìrọ̀lẹ́, àwọn èèyàn mú ọ̀pọ̀ àwọn tí ẹ̀mí èṣù ń yọ lẹ́nu wá sọ́dọ̀ rẹ̀; ọ̀rọ̀ ló fi lé àwọn ẹ̀mí náà jáde, ó sì wo gbogbo àwọn tó ń jìyà sàn, 17 kí ohun tí a sọ nípasẹ̀ wòlíì Àìsáyà lè ṣẹ, pé: “Òun fúnra rẹ̀ ru àwọn àìsàn wa, ó sì gbé àwọn àrùn wa.”+
18 Nígbà tí Jésù rí èrò tó yí i ká, ó pàṣẹ pé kí wọ́n kúrò lọ sí òdìkejì.+ 19 Akọ̀wé òfin kan wá bá a, ó sì sọ fún un pé: “Olùkọ́, màá tẹ̀ lé ọ lọ ibikíbi tí o bá lọ.”+ 20 Àmọ́ Jésù sọ fún un pé: “Àwọn kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ ní ihò, àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run sì ní ìtẹ́, àmọ́ Ọmọ èèyàn kò ní ibì kankan tó máa gbé orí rẹ̀ lé.”+ 21 Ẹlòmíì nínú àwọn ọmọ ẹ̀yìn wá sọ fún un pé: “Olúwa, gbà mí láyè kí n kọ́kọ́ lọ sìnkú bàbá mi.”+ 22 Jésù sọ fún un pé: “Máa tẹ̀ lé mi, jẹ́ kí àwọn òkú máa sin òkú wọn.”+
23 Nígbà tó wọ ọkọ̀ ojú omi, àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ tẹ̀ lé e.+ 24 Wò ó! ìjì líle bẹ̀rẹ̀ sí í jà lórí òkun, débi pé ìgbì òkun ń bo ọkọ̀ náà; àmọ́ ó ń sùn.+ 25 Ni wọ́n bá wá jí i, wọ́n sọ pé: “Olúwa, gbà wá, a ti fẹ́ ṣègbé!” 26 Ṣùgbọ́n ó sọ fún wọn pé: “Kí ló dé tí ẹ̀rù ń bà yín* tó báyìí, ẹ̀yin tí ìgbàgbọ́ yín kéré?”+ Ó wá dìde, ó sì bá ìjì àti òkun wí, ni gbogbo ẹ̀ bá pa rọ́rọ́.+ 27 Ẹnu ya àwọn ọkùnrin náà, wọ́n sì sọ pé: “Irú èèyàn wo nìyí? Ìjì àti òkun pàápàá ń gbọ́rọ̀ sí i lẹ́nu.”
28 Nígbà tó dé òdìkejì, ní agbègbè àwọn ará Gádárà, àwọn ọkùnrin méjì tí ẹ̀mí èṣù ń yọ lẹ́nu, tí wọ́n ń jáde bọ̀ láti àárín àwọn ibojì* pàdé rẹ̀.+ Wọ́n burú gan-an débi pé kò sẹ́ni tó láyà láti gba ọ̀nà yẹn kọjá. 29 Wò ó! wọ́n kígbe pé: “Kí ló pa wá pọ̀, Ọmọ Ọlọ́run?+ Ṣé o wá síbí láti fìyà jẹ wá+ kí àkókò tó tó ni?”+ 30 Ọ̀wọ́ àwọn ẹlẹ́dẹ̀ tó pọ̀ ń jẹun+ níbì kan tó jìnnà sọ́dọ̀ wọn. 31 Àwọn ẹ̀mí èṣù náà bá bẹ̀rẹ̀ sí í bẹ̀ ẹ́ pé: “Tí o bá lé wa jáde, jẹ́ ká wọnú ọ̀wọ́ àwọn ẹlẹ́dẹ̀ yẹn.”+ 32 Ó wá sọ fún wọn pé: “Ẹ lọ!” Ni wọ́n bá jáde, wọ́n sì wọnú àwọn ẹlẹ́dẹ̀ náà, wò ó! gbogbo ọ̀wọ́ ẹran náà rọ́ kọjá ní etí òkè* sínú òkun, wọ́n sì kú sínú omi. 33 Àwọn darandaran bá sá lọ, nígbà tí wọ́n dé inú ìlú, wọ́n ròyìn gbogbo ohun tó ṣẹlẹ̀, títí kan ọ̀rọ̀ àwọn ọkùnrin tí ẹ̀mí èṣù ń yọ lẹ́nu náà. 34 Wò ó! gbogbo ìlú jáde wá pàdé Jésù, nígbà tí wọ́n sì rí i, wọ́n rọ̀ ọ́ pé kó kúrò ní agbègbè wọn.+
9 Torí náà, ó wọ ọkọ̀ ojú omi, ó sì sọdá lọ sí ìlú rẹ̀.+ 2 Wò ó! wọ́n ń gbé ọkùnrin kan bọ̀ wá sọ́dọ̀ rẹ̀, ó ní àrùn rọpárọsẹ̀, ó sì dùbúlẹ̀ sórí ibùsùn. Nígbà tó rí ìgbàgbọ́ tí wọ́n ní, Jésù sọ fún alárùn rọpárọsẹ̀ náà pé: “Mọ́kàn le, ọmọ! A dárí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ jì ọ́.”+ 3 Àwọn akọ̀wé òfin kan wá ń sọ fún ara wọn pé: “Ọ̀gbẹ́ni yìí ń sọ̀rọ̀ òdì.” 4 Jésù mọ ohun tí wọ́n ń rò, ó wá sọ pé: “Kí ló dé tí ẹ̀ ń ro ohun burúkú nínú ọkàn yín?+ 5 Bí àpẹẹrẹ, èwo ló rọrùn jù, láti sọ pé, ‘A dárí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ jì ọ́,’ àbí láti sọ pé, ‘Dìde, kí o sì máa rìn’?+ 6 Àmọ́ kí ẹ lè mọ̀ pé Ọmọ èèyàn ní àṣẹ láyé láti dárí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ jini—” ó sọ fún alárùn rọpárọsẹ̀ náà pé: “Dìde, gbé ibùsùn rẹ, kí o sì máa lọ sílé rẹ.”+ 7 Ọkùnrin náà bá dìde, ó sì lọ sílé rẹ̀. 8 Nígbà tí àwọn èrò rí ohun tó ṣẹlẹ̀, ẹ̀rù bà wọ́n, wọ́n sì yin Ọlọ́run lógo, ẹni tó fún èèyàn nírú àṣẹ yìí.
9 Lẹ́yìn ìyẹn, bí Jésù ṣe ń kúrò níbẹ̀, ó tajú kán rí ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Mátíù, tó jókòó sí ọ́fíìsì àwọn agbowó orí, ó sì sọ fún un pé: “Máa tẹ̀ lé mi.” Ló bá dìde, ó sì tẹ̀ lé e.+ 10 Lẹ́yìn náà, bó ṣe ń jẹun* nínú ilé, wò ó! ọ̀pọ̀ àwọn agbowó orí àti àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ wá, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í bá Jésù àti àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ jẹun.*+ 11 Àmọ́ nígbà tí àwọn Farisí rí èyí, wọ́n sọ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Kí ló dé tí olùkọ́ yín ń bá àwọn agbowó orí àti àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ jẹun?”+ 12 Nígbà tó gbọ́ ohun tí wọ́n sọ, ó sọ pé: “Àwọn tí ara wọn le kò nílò oníṣègùn, àmọ́ àwọn tó ń ṣàìsàn nílò rẹ̀.+ 13 Torí náà, ẹ lọ kọ́ ohun tí ọ̀rọ̀ yìí túmọ̀ sí: ‘Àánú ni mo fẹ́, kì í ṣe ẹbọ.’+ Torí kì í ṣe àwọn olódodo ni mo wá pè, àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ ni.”
14 Àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jòhánù wá bá a, wọ́n sì bi í pé: “Kí ló dé tí àwa àti àwọn Farisí máa ń gbààwẹ̀ àmọ́ tí àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ kì í gbààwẹ̀?”+ 15 Jésù sọ fún wọn pé: “Kò sí ohun tó máa mú kí àwọn ọ̀rẹ́ ọkọ ìyàwó ṣọ̀fọ̀ tí ọkọ ìyàwó+ bá ṣì wà lọ́dọ̀ wọn, àbí ó wà? Àmọ́ ọjọ́ ń bọ̀, tí a máa mú ọkọ ìyàwó kúrò lọ́dọ̀ wọn,+ wọ́n máa wá gbààwẹ̀. 16 Kò sí ẹni tó máa rán ègé aṣọ tí kò tíì sún kì mọ́ ara aṣọ àwọ̀lékè tó ti gbó, torí aṣọ tuntun náà máa ya kúrò lára aṣọ àwọ̀lékè náà, ó sì máa ya ju ti tẹ́lẹ̀ lọ.+ 17 Àwọn èèyàn kì í sì í rọ wáìnì tuntun sínú àpò awọ tó ti gbó. Tí wọ́n bá ṣe bẹ́ẹ̀, àpò náà máa bẹ́, wáìnì á dà nù, àpò náà á sì bà jẹ́. Àmọ́ inú àpò awọ tuntun ni àwọn èèyàn máa ń rọ wáìnì tuntun sí, ohunkóhun ò sì ní ṣe méjèèjì.”
18 Bó ṣe ń sọ àwọn nǹkan yìí fún wọn, wò ó! alákòóso kan tó ti sún mọ́ tòsí forí balẹ̀* fún un, ó sọ pé: “Ọmọbìnrin mi á ti kú báyìí, àmọ́ wá gbé ọwọ́ rẹ lé e, ó sì máa jí.”+
19 Jésù bá dìde, òun àti àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ sì tẹ̀ lé e. 20 Wò ó! obìnrin kan tí ìsun ẹ̀jẹ̀+ ti ń yọ lẹ́nu fún ọdún méjìlá (12) sún mọ́ ọn láti ẹ̀yìn, ó sì fọwọ́ kan wajawaja tó wà létí aṣọ àwọ̀lékè rẹ̀,+ 21 torí ó ń sọ fún ara rẹ̀ ṣáá, pé: “Tí mo bá ṣáà ti fọwọ́ kan aṣọ àwọ̀lékè rẹ̀, ara mi á yá.” 22 Jésù yíjú pa dà, nígbà tó rí i, ó sọ pé: “Mọ́kàn le, ọmọbìnrin! Ìgbàgbọ́ rẹ ti mú ọ lára dá.”+ Láti wákàtí yẹn, ara obìnrin náà yá.+
23 Nígbà tó dé ilé alákòóso náà, tó sì tajú kán rí àwọn tó ń fun fèrè àtàwọn èrò tó ń pariwo,+ 24 Jésù sọ pé: “Ẹ kúrò níbẹ̀, torí ọmọdébìnrin náà ò kú, ó ń sùn ni.”+ Ni wọ́n bá bẹ̀rẹ̀ sí í rẹ́rìn-ín, wọ́n sì ń fi ṣẹlẹ́yà. 25 Gbàrà tí wọ́n ní kí àwọn èrò náà bọ́ síta, ó wọlé, ó di ọwọ́ ọmọdébìnrin náà mú,+ ọmọ náà sì dìde.+ 26 Ó dájú pé ọ̀rọ̀ yìí tàn ká gbogbo agbègbè yẹn.
27 Bí Jésù ṣe kúrò níbẹ̀, àwọn ọkùnrin afọ́jú méjì + tẹ̀ lé e, wọ́n ń kígbe pé: “Ṣàánú wa, Ọmọ Dáfídì.” 28 Lẹ́yìn tó wọnú ilé, àwọn ọkùnrin afọ́jú náà wá bá a, Jésù sì bi wọ́n pé: “Ṣé ẹ nígbàgbọ́ pé mo lè ṣe é?”+ Wọ́n dá a lóhùn pé: “Bẹ́ẹ̀ ni, Olúwa.” 29 Ó wá fọwọ́ kan ojú wọn,+ ó sọ pé: “Kó rí bẹ́ẹ̀ fún yín gẹ́gẹ́ bí ìgbàgbọ́ yín.” 30 Ojú wọn sì ríran. Lẹ́yìn náà, Jésù kìlọ̀ fún wọn gidigidi pé: “Kí ẹ rí i pé ẹnì kankan kò mọ ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí.”+ 31 Àmọ́ lẹ́yìn tí wọ́n jáde, wọ́n sọ̀rọ̀ rẹ̀ fún gbogbo èèyàn ní gbogbo agbègbè yẹn.
32 Nígbà tí wọ́n ń lọ, wò ó! àwọn èèyàn mú ọkùnrin kan tí ẹ̀mí èṣù ń yọ lẹ́nu,+ tí kò lè sọ̀rọ̀ wá sọ́dọ̀ rẹ̀; 33 lẹ́yìn tó sì lé ẹ̀mí èṣù náà jáde, ọkùnrin náà sọ̀rọ̀.+ Ẹnu ya àwọn èrò náà, wọ́n sì sọ pé: “A ò tíì rí irú èyí rí ní Ísírẹ́lì.”+ 34 Àmọ́ àwọn Farisí ń sọ pé: “Agbára alákòóso àwọn ẹ̀mí èṣù ló fi ń lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde.”+
35 Jésù wá bẹ̀rẹ̀ sí í lọ káàkiri gbogbo ìlú àti abúlé, ó ń kọ́ni nínú àwọn sínágọ́gù wọn, ó ń wàásù ìhìn rere Ìjọba náà, ó sì ń wo onírúurú àìsàn àti onírúurú àìlera sàn.+ 36 Nígbà tó rí àwọn èrò, àánú wọn ṣe é,+ torí wọ́n dà bí àgùntàn tí a bó láwọ, tí a sì fọ́n ká láìní olùṣọ́ àgùntàn.+ 37 Ó wá sọ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Òótọ́ ni, ìkórè pọ̀, àmọ́ àwọn òṣìṣẹ́ ò tó nǹkan.+ 38 Torí náà, ẹ bẹ Ọ̀gá ìkórè pé kó rán àwọn òṣìṣẹ́ jáde láti bá a kórè.”+
10 Ó pe àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ méjìlá (12), ó sì fún wọn ní àṣẹ lórí àwọn ẹ̀mí àìmọ́,+ kí wọ́n lè lé àwọn ẹ̀mí yìí jáde, kí wọ́n sì wo onírúurú àìsàn àti onírúurú àìlera sàn.
2 Orúkọ àwọn àpọ́sítélì méjìlá (12) náà nìyí:+ Àkọ́kọ́, Símónì, tí wọ́n ń pè ní Pétérù+ àti Áńdérù+ arákùnrin rẹ̀; Jémíìsì ọmọ Sébédè àti Jòhánù+ arákùnrin rẹ̀; 3 Fílípì àti Bátólómíù;+ Tọ́másì+ àti Mátíù+ agbowó orí; Jémíìsì ọmọ Áfíọ́sì; àti Tádéọ́sì; 4 Símónì tó jẹ́ Kánánéánì;* àti Júdásì Ìsìkáríọ́tù, ẹni tó dalẹ̀ rẹ̀ lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn.+
5 Àwọn méjìlá (12) yìí ni Jésù rán jáde, ó fún wọn ní àwọn ìtọ́ni yìí:+ “Ẹ má lọ sí ojú ọ̀nà àwọn orílẹ̀-èdè, ẹ má sì wọ ìlú Samáríà kankan;+ 6 kàkà bẹ́ẹ̀, léraléra ni kí ẹ máa lọ sọ́dọ̀ àwọn àgùntàn ilé Ísírẹ́lì tó sọ nù.+ 7 Bí ẹ ṣe ń lọ, ẹ máa wàásù pé: ‘Ìjọba ọ̀run ti sún mọ́lé.’+ 8 Ẹ wo àwọn aláìsàn sàn,+ ẹ jí àwọn òkú dìde, ẹ mú kí àwọn adẹ́tẹ̀ mọ́, ẹ lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde. Ọ̀fẹ́ ni ẹ gbà á, ọ̀fẹ́ ni kí ẹ fúnni. 9 Ẹ má ṣe wá wúrà, fàdákà tàbí bàbà sínú àmùrè tí ẹ̀ ń kó owó sí,+ 10 tàbí àpò oúnjẹ fún ìrìn àjò náà tàbí aṣọ méjì,* bàtà tàbí ọ̀pá,+ torí oúnjẹ tọ́ sí òṣìṣẹ́.+
11 “Tí ẹ bá wọ ìlú tàbí abúlé èyíkéyìí, ẹ wá ẹni yíyẹ kàn níbẹ̀, kí ẹ sì dúró síbẹ̀ títí ẹ fi máa kúrò.+ 12 Tí ẹ bá wọ ilé kan, ẹ kí àwọn ará ilé náà. 13 Tí ilé náà bá yẹ, kí àlàáfíà tí ẹ fẹ́ fún un wá sórí rẹ̀;+ àmọ́ tí kò bá yẹ, kí àlàáfíà látọ̀dọ̀ yín pa dà sọ́dọ̀ yín. 14 Ibikíbi tí ẹnikẹ́ni ò bá ti gbà yín tàbí fetí sí ọ̀rọ̀ yín, tí ẹ bá ń kúrò ní ilé yẹn tàbí ìlú yẹn, ẹ gbọn iyẹ̀pẹ̀ ẹsẹ̀ yín dà nù.+ 15 Lóòótọ́ ni mo sọ fún yín, ilẹ̀ Sódómù àti Gòmórà+ máa lè fara dà á ní Ọjọ́ Ìdájọ́ ju ìlú yẹn lọ.
16 “Ẹ wò ó! Mò ń rán yín jáde bí àgùntàn sáàárín àwọn ìkookò; torí náà, ẹ máa ṣọ́ra bí ejò, síbẹ̀ kí ẹ jẹ́ ọlọ́rùn mímọ́ bí àdàbà.+ 17 Ẹ máa ṣọ́ra yín lọ́dọ̀ àwọn èèyàn; torí wọ́n máa fà yín lé àwọn ilé ẹjọ́ àdúgbò lọ́wọ́,+ wọ́n á sì nà yín+ nínú àwọn sínágọ́gù wọn.+ 18 Wọ́n á tún mú yín lọ síwájú àwọn gómìnà àti àwọn ọba+ nítorí mi, kó lè jẹ́ ẹ̀rí fún wọn àti àwọn orílẹ̀-èdè.+ 19 Àmọ́ tí wọ́n bá ti fà yín lé wọn lọ́wọ́, ẹ má ṣàníyàn nípa bí ẹ ṣe máa sọ̀rọ̀ àti ohun tí ẹ máa sọ, torí a máa fún yín ní ohun tí ẹ máa sọ ní wákàtí yẹn;+ 20 torí kì í kàn ṣe ẹ̀yin lẹ̀ ń sọ̀rọ̀, àmọ́ ẹ̀mí Baba yín ló ń gbẹnu yín sọ̀rọ̀.+ 21 Bákan náà, arákùnrin máa fa arákùnrin lé ikú lọ́wọ́, bàbá máa ṣe bẹ́ẹ̀ sí ọmọ rẹ̀, àwọn ọmọ máa dìde sí àwọn òbí, wọ́n sì máa pa wọ́n.+ 22 Gbogbo èèyàn sì máa kórìíra yín nítorí orúkọ mi,+ ṣùgbọ́n ẹni tó bá fara dà á* dé òpin máa rí ìgbàlà.+ 23 Tí wọ́n bá ṣe inúnibíni sí yín ní ìlú kan, ẹ sá lọ sí òmíràn;+ torí lóòótọ́ ni mo sọ fún yín, ó dájú pé ẹ ò lè lọ yí ká àwọn ìlú Ísírẹ́lì tán títí Ọmọ èèyàn fi máa dé.
24 “Akẹ́kọ̀ọ́ ò ju olùkọ́ rẹ̀ lọ, ẹrú ò sì ju ọ̀gá rẹ̀ lọ.+ 25 Ó tó fún akẹ́kọ̀ọ́ kó dà bí olùkọ́ rẹ̀, kí ẹrú sì dà bí ọ̀gá rẹ̀.+ Tí àwọn èèyàn bá ti pe baálé ilé ní Béélísébúbù,*+ mélòómélòó wá ni àwọn ará ilé rẹ̀? 26 Torí náà, ẹ má bẹ̀rù wọn, torí kò sí nǹkan tí a bò mọ́lẹ̀ tí a ò ní tú síta, kò sì sí ohun tó jẹ́ àṣírí tí a ò ní mọ̀.+ 27 Ohun tí mo sọ fún yín nínú òkùnkùn, ẹ sọ ọ́ nínú ìmọ́lẹ̀, ohun tí ẹ sì gbọ́ tí a sọ kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́, ẹ wàásù rẹ̀ látorí ilé.+ 28 Ẹ má bẹ̀rù àwọn tó ń pa ara àmọ́ tí wọn ò lè pa ọkàn;*+ kàkà bẹ́ẹ̀, ẹ bẹ̀rù ẹni tó lè pa ọkàn àti ara run nínú Gẹ̀hẹ́nà.*+ 29 Ẹyọ owó kan tí kò fi bẹ́ẹ̀ níye lórí* ni wọ́n ń ta ológoṣẹ́ méjì, àbí bẹ́ẹ̀ kọ́? Síbẹ̀, ìkankan nínú wọn ò lè já bọ́ lulẹ̀* láìjẹ́ pé Baba yín mọ̀.+ 30 Kódà, gbogbo irun orí yín la ti kà. 31 Torí náà, ẹ má bẹ̀rù; ẹ níye lórí gan-an ju ọ̀pọ̀ ológoṣẹ́ lọ.+
32 “Nítorí náà, gbogbo ẹni tó bá fi hàn pé òun mọ̀ mí níwájú àwọn èèyàn,+ èmi náà máa fi hàn pé mo mọ̀ ọ́n níwájú Baba mi tó wà ní ọ̀run.+ 33 Àmọ́ ẹnikẹ́ni tó bá sẹ́ mi níwájú àwọn èèyàn, èmi náà máa sẹ́ ẹ níwájú Baba mi tó wà ní ọ̀run.+ 34 Ẹ má rò pé mo wá láti mú àlàáfíà wá sí ayé; ṣe ni mo wá láti mú idà wá,+ kì í ṣe àlàáfíà. 35 Torí mo wá láti fa ìpínyà, ọkùnrin sí bàbá rẹ̀, ọmọbìnrin sí ìyá rẹ̀ àti ìyàwó sí ìyá ọkọ rẹ̀.+ 36 Ní tòótọ́, àwọn ará ilé ẹni ló máa jẹ́ ọ̀tá ẹni. 37 Ẹnikẹ́ni tó bá nífẹ̀ẹ́ bàbá tàbí ìyá jù mí lọ kò yẹ fún mi; ẹnikẹ́ni tó bá sì nífẹ̀ẹ́ ọmọkùnrin tàbí ọmọbìnrin jù mí lọ kò yẹ fún mi.+ 38 Ẹnikẹ́ni tí kò bá sì gbé òpó igi oró* rẹ̀, kó sì máa tẹ̀ lé mi, kò yẹ fún mi.+ 39 Ẹnikẹ́ni tó bá rí ọkàn* rẹ̀ máa pàdánù rẹ̀, ẹnikẹ́ni tó bá sì pàdánù ọkàn* rẹ̀ nítorí mi máa rí i.+
40 “Ẹnikẹ́ni tó bá gbà yín gba èmi náà, ẹnikẹ́ni tó bá sì gbà mí gba Ẹni tó rán mi pẹ̀lú.+ 41 Ẹnikẹ́ni tó bá gba wòlíì torí pé ó jẹ́ wòlíì máa gba èrè wòlíì,+ ẹnikẹ́ni tó bá sì gba olódodo torí pé ó jẹ́ olódodo máa gba èrè olódodo. 42 Ẹnikẹ́ni tó bá fún ọ̀kan nínú àwọn ẹni kékeré yìí ní ife omi tútù lásán pé kó mu ún, torí pé ó jẹ́ ọmọ ẹ̀yìn, lóòótọ́ ni mo sọ fún yín, ó dájú pé kò ní pàdánù èrè rẹ̀.”+
11 Lẹ́yìn tí Jésù fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ méjìlá (12) ní ìtọ́ni, ó gbéra níbẹ̀ láti lọ máa kọ́ni, kó sì máa wàásù nínú àwọn ìlú wọn.+
2 Àmọ́ nínú ẹ̀wọ̀n tí Jòhánù wà,+ ó gbọ́ nípa àwọn iṣẹ́ Kristi, ó wá rán àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀+ 3 kí wọ́n lọ bi í pé: “Ṣé ìwọ ni Ẹni Tó Ń Bọ̀, àbí ká máa retí ẹlòmíì?”+ 4 Jésù dá wọn lóhùn pé: “Ẹ lọ ròyìn ohun tí ẹ̀ ń gbọ́ àti ohun tí ẹ̀ ń rí fún Jòhánù:+ 5 Àwọn afọ́jú ti ń ríran báyìí,+ àwọn arọ ń rìn, à ń wẹ àwọn adẹ́tẹ̀+ mọ́, àwọn adití ń gbọ́ràn, à ń jí àwọn òkú dìde, a sì ń sọ ìhìn rere fún àwọn aláìní.+ 6 Aláyọ̀ ni ẹni tí kò rí ohunkóhun tó máa mú kó kọsẹ̀ nínú mi.”+
7 Nígbà tí àwọn yìí ń lọ, Jésù bẹ̀rẹ̀ sí í sọ fún àwọn èrò náà nípa Jòhánù pé: “Kí lẹ jáde lọ wò ní aginjù?+ Ṣé esùsú* tí atẹ́gùn ń gbé kiri ni?+ 8 Kí wá lẹ jáde lọ wò? Ṣé ọkùnrin tó wọ aṣọ àtàtà* ni? Ṣebí inú ilé àwọn ọba ni àwọn tó wọ aṣọ àtàtà máa ń wà? 9 Ká sòótọ́, kí ló wá dé tí ẹ jáde lọ? Ṣé kí ẹ lè rí wòlíì ni? Àní mo sọ fún yín, ó ju wòlíì lọ dáadáa.+ 10 Ẹni yìí la kọ̀wé nípa rẹ̀ pé: ‘Wò ó! Màá rán ìránṣẹ́ mi ṣáájú rẹ,* ẹni tó máa ṣètò ọ̀nà rẹ dè ọ́!’+ 11 Lóòótọ́ ni mo sọ fún yín pé, nínú àwọn tí obìnrin bí, kò tíì sí ẹni tó tóbi ju Jòhánù Arinibọmi lọ, àmọ́ ẹni kékeré nínú Ìjọba ọ̀run tóbi jù ú lọ.+ 12 Láti àwọn ọjọ́ Jòhánù Arinibọmi títí di báyìí, Ìjọba ọ̀run ni ohun tí àwọn èèyàn ń fi agbára lépa, ọwọ́ àwọn tó ń sapá gidigidi sì ń tẹ̀ ẹ́.+ 13 Torí pé gbogbo wọn, àwọn Wòlíì àti Òfin, sọ ohun tó máa ṣẹlẹ̀ títí dìgbà Jòhánù;+ 14 tí ẹ bá sì fẹ́ gba èyí gbọ́, òun ni ‘Èlíjà tó máa wá.’+ 15 Kí ẹni tó bá ní etí fetí sílẹ̀.
16 “Ta ni màá fi ìran yìí wé?+ Ó dà bí àwọn ọmọ kéékèèké tí wọ́n jókòó nínú ọjà, tí wọ́n ń pe àwọn tí wọ́n jọ ń ṣeré, 17 pé: ‘A fun fèrè fún yín, àmọ́ ẹ ò jó; a pohùn réré ẹkún, àmọ́ ẹ ò kẹ́dùn, kí ẹ sì lu ara yín.’ 18 Bákan náà, Jòhánù wá, kò jẹ, kò sì mu, àmọ́ àwọn èèyàn sọ pé, ‘Ẹlẹ́mìí èṣù ni.’ 19 Ọmọ èèyàn wá, ó ń jẹ, ó sì ń mu,+ àmọ́ àwọn èèyàn sọ pé, ‘Wò ó! Ọkùnrin alájẹkì, ti kò mọ̀ ju kó mu wáìnì lọ, ọ̀rẹ́ àwọn agbowó orí àti àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀.’+ Síbẹ̀ náà, a fi ọgbọ́n hàn ní olódodo* nípasẹ̀ àwọn iṣẹ́ rẹ̀.”*+
20 Ó wá bẹ̀rẹ̀ sí í gan àwọn ìlú tó ti ṣe èyí tó pọ̀ jù nínú àwọn iṣẹ́ agbára rẹ̀, torí pé wọn ò ronú pìwà dà: 21 “O gbé, ìwọ Kórásínì! O gbé, ìwọ Bẹtisáídà! torí ká ní àwọn iṣẹ́ agbára tó ṣẹlẹ̀ nínú yín bá ṣẹlẹ̀ ní Tírè àti Sídónì ni, tipẹ́tipẹ́ ni wọ́n á ti ronú pìwà dà, nínú aṣọ ọ̀fọ̀* àti eérú.+ 22 Àmọ́ mò ń sọ fún yín pé, Tírè àti Sídónì máa lè fara dà á ní Ọjọ́ Ìdájọ́ jù yín lọ.+ 23 Àti ìwọ, Kápánáúmù,+ ṣé a máa gbé ọ ga dé ọ̀run ni? Inú Isà Òkú* nísàlẹ̀ lo máa lọ;+ torí ká ní àwọn iṣẹ́ agbára tó ṣẹlẹ̀ nínú rẹ bá ṣẹlẹ̀ ní Sódómù ni, ì bá ṣì wà títí dòní yìí. 24 Àmọ́ mo sọ fún yín pé, ilẹ̀ Sódómù máa lè fara dà á ní Ọjọ́ Ìdájọ́ jù yín lọ.”+
25 Nígbà náà, Jésù sọ pé: “Baba, Olúwa ọ̀run àti ayé, mo yìn ọ́ ní gbangba, torí pé o fi àwọn nǹkan yìí pa mọ́ fún àwọn ọlọ́gbọ́n àti àwọn amòye, o sì ti ṣí wọn payá fún àwọn ọmọdé.+ 26 Bẹ́ẹ̀ ni, Baba, torí pé ohun tí o fọwọ́ sí nìyí. 27 Baba mi ti fa ohun gbogbo lé mi lọ́wọ́,+ kò sì sẹ́ni tó mọ Ọmọ délẹ̀délẹ̀ àfi Baba;+ bẹ́ẹ̀ ni kò sẹ́ni tó mọ Baba délẹ̀délẹ̀ àfi Ọmọ àti ẹnikẹ́ni tí Ọmọ bá fẹ́ ṣí i payá fún.+ 28 Ẹ wá sọ́dọ̀ mi, gbogbo ẹ̀yin tó ń ṣe làálàá, tí a di ẹrù wọ̀ lọ́rùn, màá sì tù yín lára. 29 Ẹ gba àjàgà mi sọ́rùn yín, kí ẹ sì kẹ́kọ̀ọ́ lọ́dọ̀ mi, torí oníwà tútù àti ẹni tó rẹlẹ̀ ní ọkàn ni mí,+ ara sì máa tù yín.* 30 Torí àjàgà mi rọrùn,* ẹrù mi sì fúyẹ́.”
12 Ní àkókò yẹn, Jésù gba oko ọkà kọjá ní Sábáàtì. Ebi wá ń pa àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í ya àwọn erín ọkà* jẹ.+ 2 Nígbà tí àwọn Farisí rí èyí, wọ́n sọ fún un pé: “Wò ó! Àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ ń ṣe ohun tí kò bófin mu lọ́jọ́ Sábáàtì.”+ 3 Ó sọ fún wọn pé: “Ṣé ẹ ò tíì ka ohun tí Dáfídì ṣe nígbà tí ebi ń pa òun àti àwọn ọkùnrin tó wà pẹ̀lú rẹ̀?+ 4 Bó ṣe wọ ilé Ọlọ́run, tí wọ́n sì jẹ àwọn búrẹ́dì tí wọ́n ń gbé síwájú,*+ èyí tí kò bófin mu fún òun àti àwọn tó wà pẹ̀lú rẹ̀ láti jẹ, àfi àwọn àlùfáà nìkan?+ 5 Àbí ẹ ò tíì kà á nínú Òfin pé ní àwọn Sábáàtì, àwọn àlùfáà inú tẹ́ńpìlì sọ Sábáàtì di aláìmọ́, a ò sì dá wọn lẹ́bi?+ 6 Àmọ́ mo sọ fún yín pé ohun kan tó tóbi ju tẹ́ńpìlì lọ wà níbí.+ 7 Ṣùgbọ́n ká ní ẹ mọ ohun tí ọ̀rọ̀ yìí túmọ̀ sí ni, ‘Àánú ni mo fẹ́,+ kì í ṣe ẹbọ,’+ ẹ ò ní dá àwọn tí kò jẹ̀bi lẹ́bi. 8 Torí Ọmọ èèyàn ni Olúwa Sábáàtì.”+
9 Lẹ́yìn tó kúrò níbẹ̀, ó lọ sínú sínágọ́gù wọn, 10 wò ó! ọkùnrin kan wà tí ọwọ́ rẹ̀ rọ!+ Kí wọ́n lè fẹ̀sùn kàn án, wọ́n bi í pé, “Ṣé ó bófin mu láti ṣe ìwòsàn ní Sábáàtì?”+ 11 Ó sọ fún wọn pé: “Tí ẹ bá ní àgùntàn kan, tí àgùntàn náà sì já sínú kòtò ní Sábáàtì, ṣé ẹnì kan wà nínú yín tí kò ní dì í mú, kó sì gbé e jáde?+ 12 Ṣé èèyàn ò wá ṣeyebíye ju àgùntàn lọ? Torí náà, ó bófin mu láti ṣe ohun tó dáa ní Sábáàtì.” 13 Ó wá sọ fún ọkùnrin náà pé: “Na ọwọ́ rẹ.” Ó na ọwọ́ rẹ̀, ó sì pa dà rí bíi ti ọwọ́ kejì. 14 Àmọ́ àwọn Farisí jáde lọ, wọ́n sì gbìmọ̀ pọ̀ láti pa á. 15 Nígbà tí Jésù mọ èyí, ó kúrò níbẹ̀. Ọ̀pọ̀ èèyàn tún tẹ̀ lé e,+ ó sì wo gbogbo wọn sàn, 16 àmọ́ ó kìlọ̀ fún wọn gidigidi pé kí wọ́n má ṣe jẹ́ kí àwọn èèyàn mọ òun,+ 17 kí ohun tí a sọ nípasẹ̀ wòlíì Àìsáyà lè ṣẹ, ẹni tó sọ pé:
18 “Wò ó! Ìránṣẹ́ mi+ tí mo yàn, àyànfẹ́ mi, ẹni tí mo* tẹ́wọ́ gbà!+ Màá fi ẹ̀mí mi sára rẹ̀,+ ó sì máa jẹ́ kí ìdájọ́ òdodo ṣe kedere sí àwọn orílẹ̀-èdè. 19 Kò ní jiyàn,+ kò ní pariwo, ẹnikẹ́ni ò sì ní gbọ́ ohùn rẹ̀ láwọn ọ̀nà tó wà ní gbangba. 20 Kò ní fọ́ esùsú* kankan tó ti ṣẹ́, kò sì ní pa òwú àtùpà kankan tó ń jó lọ́úlọ́ú,+ tí wọ́n fi ọ̀gbọ̀ ṣe, títí ó fi máa ṣe ìdájọ́ òdodo láṣeyọrí. 21 Ní tòótọ́, àwọn orílẹ̀-èdè máa ní ìrètí nínú orúkọ rẹ̀.”+
22 Lẹ́yìn náà, wọ́n mú ọkùnrin kan tí ẹ̀mí èṣù ń yọ lẹ́nu wá sọ́dọ̀ rẹ̀, ọkùnrin náà fọ́jú, kò sì lè sọ̀rọ̀. Ó wo ọkùnrin náà sàn, ọkùnrin náà wá bẹ̀rẹ̀ sí í sọ̀rọ̀, ó sì ń ríran. 23 Ó ya gbogbo èrò náà lẹ́nu, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í sọ pé: “Ṣé kì í ṣe Ọmọ Dáfídì nìyí?” 24 Nígbà tí àwọn Farisí gbọ́ èyí, wọ́n sọ pé: “Ọ̀gbẹ́ni yìí kò lè lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde, tí kò bá ní agbára Béélísébúbù,* alákòóso àwọn ẹ̀mí èṣù.”+ 25 Jésù mọ ohun tí wọ́n ń rò, ó wá sọ fún wọn pé: “Gbogbo ìjọba tó bá pínyà sí ara rẹ̀ máa pa run, gbogbo ìlú tàbí ilé tó bá sì pínyà sí ara rẹ̀ kò ní dúró. 26 Lọ́nà kan náà, tí Sátánì bá ń lé Sátánì jáde, ó ti pínyà sí ara rẹ̀ nìyẹn; báwo ni ìjọba rẹ̀ ṣe máa wá dúró? 27 Bákan náà, tó bá jẹ́ agbára Béélísébúbù ni mo fi ń lé ẹ̀mí èṣù jáde, agbára ta ni àwọn ọmọ yín fi ń lé wọn jáde? Ìdí nìyí tí wọ́n fi máa jẹ́ adájọ́ yín. 28 Àmọ́ tó bá jẹ́ ẹ̀mí Ọlọ́run ni mo fi ń lé ẹ̀mí èṣù jáde, Ìjọba Ọlọ́run ti dé bá yín lójijì lóòótọ́.+ 29 Àbí báwo ni ẹnì kan ṣe lè gbógun wọ ilé ọkùnrin alágbára, kó sì fipá gba àwọn ohun ìní rẹ̀, tí kò bá kọ́kọ́ de ọkùnrin alágbára náà mọ́lẹ̀? Ìgbà yẹn ló máa tó lè kó o lẹ́rù nínú ilé rẹ̀. 30 Ẹnikẹ́ni tí kò bá sí lọ́dọ̀ mi ń ta kò mí, ẹnikẹ́ni tí kò bá sì dara pọ̀ mọ́ mi ń fọ́n ká.+
31 “Nítorí èyí, mò ń sọ fún yín pé, gbogbo oríṣiríṣi ẹ̀ṣẹ̀ àti ọ̀rọ̀ òdì la máa dárí rẹ̀ ji àwọn èèyàn, àmọ́ ọ̀rọ̀ òdì sí ẹ̀mí kò ní ìdáríjì.+ 32 Bí àpẹẹrẹ, ẹnikẹ́ni tó bá sọ̀rọ̀ òdì sí Ọmọ èèyàn máa rí ìdáríjì;+ àmọ́ ẹnikẹ́ni tó bá sọ̀rọ̀ òdì sí ẹ̀mí mímọ́, kò ní rí ìdáríjì, àní, nínú ètò àwọn nǹkan yìí* tàbí èyí tó ń bọ̀.+
33 “Nínú kí ẹ mú kí igi dára, kí èso rẹ̀ sì dára, àbí kí ẹ mú kí igi jẹrà, kí èso rẹ̀ sì jẹrà, torí èso igi la fi ń mọ igi.+ 34 Ẹ̀yin ọmọ paramọ́lẹ̀,+ báwo lẹ ṣe lè sọ àwọn ohun tó dáa nígbà tó jẹ́ pé ẹni burúkú ni yín? Torí lára ọ̀pọ̀ nǹkan tó wà nínú ọkàn ni ẹnu ń sọ.+ 35 Ẹni rere máa ń mú ohun rere jáde látinú ìṣúra rere rẹ̀, àmọ́ ẹni burúkú máa ń mú ohun burúkú jáde látinú ìṣúra burúkú rẹ̀.+ 36 Mò ń sọ fún yín pé ní Ọjọ́ Ìdájọ́, àwọn èèyàn máa jíhìn+ gbogbo ọ̀rọ̀ tí kò wúlò tí wọ́n sọ; 37 torí ọ̀rọ̀ yín la máa fi pè yín ní olódodo, ọ̀rọ̀ yín la sì máa fi dá yín lẹ́bi.”
38 Àwọn kan lára àwọn akọ̀wé òfin àti àwọn Farisí wá fún un lésì pé: “Olùkọ́, a fẹ́ rí àmì kan látọ̀dọ̀ rẹ.”+ 39 Ó sọ fún wọn pé: “Ìran burúkú àti alágbèrè* kò yéé wá àmì, àmọ́ a ò ní fún un ní àmì kankan àfi àmì wòlíì Jónà.+ 40 Bí Jónà ṣe wà nínú ikùn ẹja ńlá náà fún ọjọ́ mẹ́ta,*+ bẹ́ẹ̀ náà ni Ọmọ èèyàn máa wà ní àárín ilẹ̀ fún ọjọ́ mẹ́ta.+ 41 Àwọn ará Nínéfè máa dìde láti ṣèdájọ́ ìran yìí, wọ́n á sì dá a lẹ́bi, torí pé wọ́n ronú pìwà dà nígbà tí Jónà wàásù fún wọn.+ Àmọ́ ẹ wò ó! ohun kan tó ju Jónà lọ wà níbí.+ 42 A máa gbé ọbabìnrin gúúsù dìde láti ṣèdájọ́ ìran yìí, ó sì máa dá a lẹ́bi, torí ó wá láti ìkángun ayé kó lè gbọ́ ọ̀rọ̀ ọgbọ́n Sólómọ́nì.+ Àmọ́ ẹ wò ó! ohun kan tó ju Sólómọ́nì lọ wà níbí.+
43 “Tí ẹ̀mí àìmọ́ kan bá jáde nínú ẹnì kan, á gba àwọn ibi tí kò lómi kọjá láti wá ibi ìsinmi, àmọ́ kò ní rí ìkankan.+ 44 Á wá sọ pé, ‘Màá pa dà lọ sí ilé mi tí mo ti kúrò,’ tó bá sì dé, á rí i pé ilé náà ṣófo, àmọ́ wọ́n ti gbá a mọ́, wọ́n sì ṣe é lọ́ṣọ̀ọ́. 45 Á wá lọ mú ẹ̀mí méje míì dání, tí wọ́n burú ju òun fúnra rẹ̀ lọ, lẹ́yìn tí wọ́n bá sì wọlé, wọ́n á máa gbé ibẹ̀; ipò ẹni yẹn nígbẹ̀yìn á wá burú ju ti tẹ́lẹ̀ lọ.+ Bó ṣe máa rí fún ìran burúkú yìí náà nìyẹn.”
46 Nígbà tó ṣì ń bá àwọn èrò náà sọ̀rọ̀ lọ́wọ́, ìyá rẹ̀ àti àwọn arákùnrin rẹ̀+ dúró síta, wọ́n ń wá bí wọ́n ṣe máa bá a sọ̀rọ̀.+ 47 Ẹnì kan wá sọ fún un pé: “Wò ó! Ìyá rẹ àti àwọn arákùnrin rẹ ń dúró níta, wọ́n fẹ́ bá ọ sọ̀rọ̀.” 48 Ó dá ẹni tó bá a sọ̀rọ̀ lóhùn pé: “Ta ni ìyá mi, ta sì ni àwọn arákùnrin mi?” 49 Ó wá na ọwọ́ rẹ̀ sí àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀, ó sọ pé: “Wò ó! Ìyá mi àti àwọn arákùnrin mi!+ 50 Torí ẹnikẹ́ni tó bá ń ṣe ìfẹ́ Baba mi tó wà ní ọ̀run, ẹni yẹn ni arákùnrin mi, arábìnrin mi àti ìyá mi.”+
13 Lọ́jọ́ yẹn, Jésù kúrò nínú ilé, ó sì jókòó sétí òkun. 2 Ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn kóra jọ sọ́dọ̀ rẹ̀ débi pé ó wọ ọkọ̀ ojú omi, ó jókòó, gbogbo àwọn èrò náà sì dúró sí etíkun.+ 3 Ó wá fi àpèjúwe sọ ọ̀pọ̀lọpọ̀ nǹkan fún wọn,+ ó ní: “Ẹ wò ó! Afúnrúgbìn kan jáde lọ fún irúgbìn.+ 4 Bó ṣe ń fún irúgbìn, díẹ̀ já bọ́ sí etí ọ̀nà, àwọn ẹyẹ wá, wọ́n sì ṣà á jẹ.+ 5 Àwọn míì já bọ́ sórí ilẹ̀ àpáta tí kò fi bẹ́ẹ̀ sí iyẹ̀pẹ̀, wọ́n sì hù lójú ẹsẹ̀ torí pé iyẹ̀pẹ̀ náà ò jìn.+ 6 Àmọ́ nígbà tí oòrùn ràn, ó jó wọn gbẹ, wọ́n sì rọ torí pé wọn ò ní gbòǹgbò. 7 Àwọn míì já bọ́ sáàárín ẹ̀gún, àwọn ẹ̀gún náà yọ, wọ́n sì fún wọn pa.+ 8 Síbẹ̀ àwọn míì já bọ́ sórí iyẹ̀pẹ̀ tó dáa, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í so èso, eléyìí so ní ìlọ́po ọgọ́rùn-ún (100), ìyẹn ọgọ́ta (60), òmíràn ọgbọ̀n (30).+ 9 Kí ẹni tó bá ní etí fetí sílẹ̀.”+
10 Àwọn ọmọ ẹ̀yìn wá bá a, wọ́n sì sọ fún un pé: “Kí ló dé tí ò ń fi àpèjúwe bá wọn sọ̀rọ̀?”+ 11 Ó sọ fún wọn pé: “Ẹ̀yin la yọ̀ǹda fún pé kí ẹ lóye àwọn àṣírí mímọ́+ Ìjọba ọ̀run, àmọ́ a ò yọ̀ǹda fún wọn. 12 Torí ẹnikẹ́ni tó bá ní, a máa fi kún ohun tó ní, a sì máa mú kó ní púpọ̀; àmọ́ ẹnikẹ́ni tí kò bá ní, a máa gba ohun tó ní pàápàá kúrò lọ́wọ́ rẹ̀.+ 13 Ìdí nìyẹn tí mo fi ń fi àpèjúwe bá wọn sọ̀rọ̀; torí ní ti bí wọ́n ṣe ń wò, lásán ni wọ́n ń wò, ní ti bí wọ́n ṣe ń gbọ́, lásán ni wọ́n ń gbọ́, kò sì yé wọn.+ 14 Àsọtẹ́lẹ̀ Àìsáyà sì ṣẹ sí wọn lára. Ó sọ pé: ‘Ó dájú pé ẹ máa gbọ́, àmọ́ kò ní yé yín rárá, ó sì dájú pé ẹ máa wò, àmọ́ ẹ ò ní ríran rárá.+ 15 Torí ọkàn àwọn èèyàn yìí ti yigbì, wọ́n sì ti fi etí wọn gbọ́, àmọ́ wọn ò dáhùn, wọ́n ti di ojú wọn, kí wọ́n má bàa fi ojú wọn ríran láé, kí wọ́n má sì fi etí wọn gbọ́, kó má sì yé wọn nínú ọkàn wọn, kí wọ́n lè yí pa dà, kí n sì mú wọn lára dá.’+
16 “Àmọ́, aláyọ̀ ni ojú yín torí wọ́n rí àti etí yín torí wọ́n gbọ́.+ 17 Lóòótọ́ ni mo sọ fún yín pé, ó wu ọ̀pọ̀ àwọn wòlíì àti àwọn olódodo pé kí wọ́n rí àwọn ohun tí ẹ̀ ń rí, àmọ́ wọn ò rí i,+ ó wù wọ́n kí wọ́n gbọ́ àwọn ohun tí ẹ̀ ń gbọ́, àmọ́ wọn ò gbọ́ ọ.
18 “Ní báyìí, ẹ fetí sí àpèjúwe ọkùnrin tó fún irúgbìn.+ 19 Tí ẹnikẹ́ni bá gbọ́ ọ̀rọ̀ Ìjọba náà, àmọ́ tí kò yé e, ẹni burúkú náà+ á wá, á sì já ohun tí a gbìn sínú ọkàn rẹ̀ gbà lọ; èyí ni irúgbìn tó bọ́ sí etí ọ̀nà.+ 20 Ní ti èyí tó bọ́ sórí ilẹ̀ àpáta, òun ló ń gbọ́ ọ̀rọ̀ náà, tó sì fi ayọ̀ tẹ́wọ́ gbà á lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀.+ 21 Síbẹ̀, kò ta gbòǹgbò nínú rẹ̀, àmọ́ ó ń bá a lọ fúngbà díẹ̀, lẹ́yìn tí ìpọ́njú tàbí inúnibíni sì dé nítorí ọ̀rọ̀ náà, ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ni a mú un kọsẹ̀. 22 Ní ti èyí tó bọ́ sáàárín àwọn ẹ̀gún, òun ló ń gbọ́ ọ̀rọ̀ náà, àmọ́ tí àníyàn ètò àwọn nǹkan yìí*+ àti agbára ìtannijẹ ọrọ̀ fún ọ̀rọ̀ náà pa, kò sì so èso.+ 23 Ní ti èyí tó bọ́ sórí iyẹ̀pẹ̀ tó dáa, òun ló ń gbọ́ ọ̀rọ̀ náà, tó sì ń yé e, tó so èso lóòótọ́, tó sì ń mú èso jáde, eléyìí so ní ìlọ́po ọgọ́rùn-ún (100), ìyẹn ọgọ́ta (60), òmíràn ọgbọ̀n (30).”+
24 Ó sọ àpèjúwe míì fún wọn, ó ní: “A lè fi Ìjọba ọ̀run wé ọkùnrin kan tó fún irúgbìn tó dáa sínú pápá rẹ̀. 25 Nígbà tí àwọn èèyàn ń sùn, ọ̀tá rẹ̀ wá, ó gbin èpò sí àárín àlìkámà* náà, ó sì lọ. 26 Nígbà tí ohun ọ̀gbìn náà hù, tó sì so èso, àwọn èpò náà fara hàn. 27 Àwọn ẹrú baálé ilé náà wá, wọ́n sì sọ fún un pé, ‘Ọ̀gá, ṣebí irúgbìn tó dáa lo gbìn sínú pápá rẹ? Báwo ló ṣe wá ní èpò?’ 28 Ó sọ fún wọn pé, ‘Ọkùnrin kan tó jẹ́ ọ̀tá ló ṣe èyí.’+ Àwọn ẹrú náà sọ fún un pé, ‘Ṣé o fẹ́ ká lọ kó wọn jọ ni?’ 29 Ó sọ pé, ‘Rárá, torí kí ẹ má bàa hú àlìkámà pẹ̀lú èpò nígbà tí ẹ bá ń kó èpò jọ. 30 Ẹ jẹ́ kí méjèèjì jọ dàgbà títí dìgbà ìkórè, tó bá wá dìgbà ìkórè, màá sọ fún àwọn tó ń kórè pé: Ẹ kọ́kọ́ kó àwọn èpò jọ, kí ẹ sì dì wọ́n ní ìdìpọ̀-ìdìpọ̀ láti sun wọ́n; kí ẹ wá kó àlìkámà jọ sínú ilé ìkẹ́rùsí mi.’”+
31 Ó sọ àpèjúwe míì fún wọn, ó ní: “Ìjọba ọ̀run dà bíi hóró músítádì kan, tí ọkùnrin kan mú, tó sì gbìn sínú pápá rẹ̀.+ 32 Ní tòótọ́, òun ló kéré jù lọ nínú gbogbo irúgbìn, àmọ́ tó bá ti dàgbà, òun ló máa ń tóbi jù lọ nínú àwọn ohun ọ̀gbìn, á sì di igi, débi pé àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run á wá máa gbé láàárín àwọn ẹ̀ka rẹ̀.”
33 Ó sọ àpèjúwe míì fún wọn, ó ní: “Ìjọba ọ̀run dà bí ìwúkàrà, èyí tí obìnrin kan mú, tó sì pò mọ́ ìyẹ̀fun tó kún òṣùwọ̀n ńlá mẹ́ta, títí gbogbo rẹ̀ fi wú.”+
34 Gbogbo nǹkan yìí ni Jésù fi àpèjúwe sọ fún àwọn èrò náà. Ní tòótọ́, kì í bá wọn sọ̀rọ̀ láìlo àpèjúwe,+ 35 kí ohun tí a sọ nípasẹ̀ wòlíì lè ṣẹ, ẹni tó sọ pé: “Màá la ẹnu mi láti sọ àpèjúwe; màá kéde àwọn ohun tó pa mọ́ láti ìbẹ̀rẹ̀.”*+
36 Lẹ́yìn tó ní kí àwọn èrò náà máa lọ, ó wọnú ilé. Àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ wá bá a, wọ́n sì sọ pé: “Ṣàlàyé àpèjúwe àwọn èpò inú pápá fún wa.” 37 Ó dá wọn lóhùn pé: “Ọmọ èèyàn ni ẹni tó fún irúgbìn tó dáa; 38 ayé ni pápá náà.+ Ní ti irúgbìn tó dáa, àwọn yìí ni àwọn ọmọ Ìjọba náà, àmọ́ àwọn ọmọ ẹni burúkú náà ni èpò,+ 39 Èṣù sì ni ọ̀tá tó gbìn wọ́n. Ìparí ètò àwọn nǹkan* ni ìgbà ìkórè, àwọn áńgẹ́lì sì ni olùkórè. 40 Torí náà, bí a ṣe kó àwọn èpò jọ, tí a sì dáná sun wọ́n, bẹ́ẹ̀ ló ṣe máa rí ní ìparí ètò àwọn nǹkan.*+ 41 Ọmọ èèyàn máa rán àwọn áńgẹ́lì rẹ̀, wọ́n sì máa kó gbogbo ohun tó ń fa ìkọ̀sẹ̀ àti àwọn arúfin jáde kúrò nínú Ìjọba rẹ̀, 42 wọ́n sì máa jù wọ́n sínú iná ìléru.+ Ibẹ̀ ni wọ́n á ti máa sunkún, tí wọ́n á sì ti máa payín keke. 43 Ní àkókò yẹn, àwọn olódodo máa tàn yòò bí oòrùn+ nínú Ìjọba Baba wọn. Kí ẹni tó bá ní etí fetí sílẹ̀.
44 “Ìjọba ọ̀run dà bí ìṣúra tí a fi pa mọ́ sínú pápá, èyí tí ọkùnrin kan rí, tó sì fi pa mọ́; torí pé inú rẹ̀ ń dùn, ó lọ ta gbogbo ohun tó ní, ó sì ra pápá yẹn.+
45 “Ìjọba ọ̀run tún dà bí oníṣòwò kan tó ń rìnrìn àjò, tó ń wá àwọn péálì tó dáa. 46 Nígbà tó rí péálì kan tó níye lórí gan-an, ó lọ, ó sì yára ta gbogbo ohun tó ní, ó sì rà á.+
47 “Ìjọba ọ̀run tún dà bí àwọ̀n ńlá kan, tí wọ́n jù sínú òkun, tó sì kó oríṣiríṣi ẹja. 48 Nígbà tó kún, wọ́n fà á gòkè sí etíkun, wọ́n wá jókòó, wọ́n kó àwọn tó dáa+ sínú àwọn ohun èlò, àmọ́ wọ́n da èyí tí kò dáa+ nù. 49 Bó ṣe máa rí ní ìparí ètò àwọn nǹkan* nìyẹn. Àwọn áńgẹ́lì máa jáde lọ, wọ́n á ya àwọn ẹni burúkú sọ́tọ̀ kúrò lára àwọn olódodo, 50 wọ́n sì máa jù wọ́n sínú iná ìléru. Ibẹ̀ ni wọ́n á ti máa sunkún, tí wọ́n á sì ti máa payín keke.
51 “Ṣé gbogbo nǹkan yìí yé yín?” Wọ́n sọ fún un pé: “Bẹ́ẹ̀ ni.” 52 Ó wá sọ fún wọn pé: “Tó bá rí bẹ́ẹ̀, gbogbo ẹni tó ń kọ́ni ní gbangba, tí a kọ́ nípa Ìjọba ọ̀run, dà bí ọkùnrin kan tó jẹ́ baálé ilé, tó kó àwọn ohun tuntun àti ohun àtijọ́ jáde látinú ibi tó ń kó ìṣúra sí.”
53 Nígbà tí Jésù sọ àwọn àpèjúwe yìí tán, ó kúrò níbẹ̀. 54 Lẹ́yìn tó dé agbègbè ìlú rẹ̀,+ ó bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ wọn nínú sínágọ́gù wọn, débi pé ó yà wọ́n lẹ́nu, wọ́n sì sọ pé: “Ibo ni ọkùnrin yìí ti rí ọgbọ́n yìí àti àwọn iṣẹ́ agbára yìí?+ 55 Àbí ọmọ káfíńtà kọ́ nìyí?+ Ṣebí Màríà lorúkọ ìyá rẹ̀, Jémíìsì, Jósẹ́fù, Símónì àti Júdásì sì ni àwọn arákùnrin rẹ̀?+ 56 Ṣebí gbogbo àwọn arábìnrin rẹ̀ ló wà pẹ̀lú wa? Ibo ló ti wá rí gbogbo èyí?”+ 57 Torí náà, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í kọsẹ̀ nítorí rẹ̀.+ Ṣùgbọ́n Jésù sọ fún wọn pé: “Wòlíì máa ń níyì, àmọ́ kì í gbayì ní ìlú rẹ̀ àti ní ilé òun fúnra rẹ̀.”+ 58 Kò sì ṣe ọ̀pọ̀ iṣẹ́ agbára níbẹ̀ torí pé wọn ò nígbàgbọ́.
14 Ní àkókò yẹn, Hẹ́rọ́dù, alákòóso agbègbè náà,* gbọ́ ìròyìn nípa Jésù,+ 2 ó sì sọ fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pé: “Jòhánù Arinibọmi nìyí. A ti jí i dìde, ìdí sì nìyẹn tó fi lè ṣe àwọn iṣẹ́ agbára yìí.”+ 3 Hẹ́rọ́dù* ti mú Jòhánù, ó dè é, ó sì fi sẹ́wọ̀n torí Hẹrodíà, ìyàwó Fílípì arákùnrin rẹ̀.+ 4 Jòhánù sì ti ń sọ fún un pé: “Kò bófin mu fún ọ láti fẹ́ obìnrin yìí.”+ 5 Àmọ́, bó tiẹ̀ jẹ́ pé ó fẹ́ pa á, ó ń bẹ̀rù àwọn èèyàn, torí pé wòlíì ni wọ́n kà á sí.+ 6 Àmọ́ nígbà tí wọ́n ń ṣe ayẹyẹ ọjọ́ ìbí+ Hẹ́rọ́dù, ọmọbìnrin Hẹrodíà jó níbi ayẹyẹ náà, ó sì múnú Hẹ́rọ́dù dùn gan-an+ 7 débi pé ó ṣèlérí, ó sì búra pé òun máa fún un ní ohunkóhun tó bá béèrè. 8 Ìyá ọmọbìnrin náà kọ́ ọ ní ohun tó máa sọ, ó sì sọ pé: “Fún mi ní orí Jòhánù Arinibọmi níbí yìí nínú àwo pẹrẹsẹ.”+ 9 Bó tiẹ̀ jẹ́ pé inú ọba ò dùn rárá, ó pàṣẹ pé kí wọ́n fún un, torí pé ó ti búra àti torí àwọn tó ń bá a jẹun.* 10 Ó wá ránṣẹ́ pé kí wọ́n lọ bẹ́ orí Jòhánù nínú ẹ̀wọ̀n. 11 Wọ́n gbé orí rẹ̀ wá nínú àwo pẹrẹsẹ, wọ́n sì fún ọmọbìnrin náà, ó wá gbé e wá fún ìyá rẹ̀. 12 Lẹ́yìn náà, àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ wá gbé òkú rẹ̀ kúrò, wọ́n sì sin ín; wọ́n wá ròyìn ohun tó ṣẹlẹ̀ fún Jésù. 13 Nígbà tí Jésù gbọ́ ohun tó ṣẹlẹ̀, ó wọ ọkọ̀ ojú omi kúrò níbẹ̀ lọ sí ibi tó dá, kó lè dá wà. Ṣùgbọ́n nígbà tí àwọn èrò gbọ́ nípa rẹ̀, wọ́n fi ẹsẹ̀ rìn tẹ̀ lé e látinú àwọn ìlú.+
14 Nígbà tó wá sí etíkun, ó rí èrò rẹpẹtẹ, àánú wọn ṣe é,+ ó sì wo àwọn tó ń ṣàìsàn nínú wọn sàn.+ 15 Àmọ́ nígbà tó di ìrọ̀lẹ́, àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ wá sọ́dọ̀ rẹ̀, wọ́n sì sọ pé: “Ibí yìí dá, ọjọ́ sì ti lọ; jẹ́ kí àwọn èèyàn yìí máa lọ, kí wọ́n lè lọ sínú àwọn abúlé, kí wọ́n sì ra ohun tí wọ́n máa jẹ.”+ 16 Ṣùgbọ́n Jésù sọ fún wọn pé: “Wọn ò nílò kí wọ́n lọ; ẹ fún wọn ní nǹkan tí wọ́n máa jẹ.” 17 Wọ́n sọ fún un pé: “A ò ní nǹkan kan níbí àfi búrẹ́dì márùn-ún àti ẹja méjì.” 18 Ó sọ pé: “Ẹ mú un wá síbí fún mi.” 19 Ó wá sọ fún àwọn èrò náà pé kí wọ́n jókòó* sórí koríko. Lẹ́yìn náà, ó mú búrẹ́dì márùn-ún àti ẹja méjì náà, ó wo ojú ọ̀run, ó sì súre,+ lẹ́yìn tó bu búrẹ́dì náà, ó fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn, àwọn ọmọ ẹ̀yìn sì fún àwọn èrò náà. 20 Gbogbo wọn jẹ, wọ́n yó, wọ́n sì kó èyí tó ṣẹ́ kù jọ, ó kún apẹ̀rẹ̀ méjìlá (12).+ 21 Àwọn tó jẹun tó nǹkan bí ẹgbẹ̀rún márùn-ún (5,000) ọkùnrin pẹ̀lú àwọn obìnrin àti àwọn ọmọdé.+ 22 Láìjáfara, ó mú kí àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ wọ ọkọ̀ ojú omi, kí wọ́n sì lọ ṣáájú rẹ̀ sí etíkun tó wà ní òdìkejì, ó sì ní kí àwọn èrò náà máa lọ.+
23 Lẹ́yìn tó ní kí àwọn èrò náà máa lọ, òun nìkan lọ sórí òkè láti gbàdúrà.+ Nígbà tó di ìrọ̀lẹ́, òun nìkan ló wà níbẹ̀. 24 Ní àkókò yẹn, ọkọ̀ ojú omi náà ti wà ní ọ̀pọ̀ ọgọ́rọ̀ọ̀rún ìwọ̀n yáàdì* sí orí ilẹ̀, wọ́n ń bá ìgbì òkun fà á, torí pé atẹ́gùn náà ń dà wọ́n láàmú. 25 Àmọ́ ní ìṣọ́ kẹrin òru,* ó wá bá wọn, ó ń rìn lórí òkun. 26 Nígbà tí wọ́n tajú kán rí i tó ń rìn lórí òkun, ọkàn àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ò balẹ̀, wọ́n sọ pé: “Ìran abàmì nìyí!” Wọ́n bá kígbe torí ẹ̀rù bà wọ́n. 27 Àmọ́ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, Jésù sọ fún wọn pé: “Ẹ mọ́kàn le! Èmi ni; ẹ má bẹ̀rù.”+ 28 Pétérù sọ fún un pé: “Olúwa, tó bá jẹ́ ìwọ ni, pàṣẹ fún mi pé kí n wá bá ọ lórí omi.” 29 Ó sọ pé: “Máa bọ̀!” Pétérù wá jáde nínú ọkọ̀ ojú omi, ó rìn lórí omi, ó sì ń lọ sọ́dọ̀ Jésù. 30 Àmọ́ nígbà tó wo ìjì tó ń jà, ẹ̀rù bà á. Nígbà tó bẹ̀rẹ̀ sí í rì, ó ké jáde pé: “Olúwa, gbà mí!” 31 Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, Jésù na ọwọ́ rẹ̀, ó sì dì í mú, ó sọ fún un pé: “Ìwọ tí ìgbàgbọ́ rẹ kéré, kí ló dé tí o fi ṣiyèméjì?”+ 32 Lẹ́yìn tí wọ́n wọnú ọkọ̀ ojú omi náà, ìjì tó ń jà rọlẹ̀. 33 Àwọn tó wà nínú ọkọ̀ ojú omi náà wá tẹrí ba* fún un, wọ́n sọ pé: “Ọmọ Ọlọ́run ni ọ́ lóòótọ́.” 34 Wọ́n sọdá, wọ́n sì gúnlẹ̀ sí Jẹ́nẹ́sárẹ́tì.+
35 Nígbà tí àwọn èèyàn ibẹ̀ wá mọ̀ pé òun ni, wọ́n ránṣẹ́ sí gbogbo ìgbèríko tó wà ní àyíká yẹn, àwọn èèyàn sì mú gbogbo àwọn tó ń ṣàìsàn wá sọ́dọ̀ rẹ̀. 36 Wọ́n bẹ̀ ẹ́ pé kí àwọn ṣáà fọwọ́ kan wajawaja tó wà létí aṣọ àwọ̀lékè rẹ̀,+ ara gbogbo àwọn tó fọwọ́ kàn án sì yá pátápátá.
15 Lẹ́yìn náà, àwọn Farisí àti àwọn akọ̀wé òfin+ wá sọ́dọ̀ Jésù láti Jerúsálẹ́mù, wọ́n sọ pé: 2 “Kí ló dé tí àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ ò tẹ̀ lé àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ àwọn èèyàn àtijọ́? Bí àpẹẹrẹ, wọn kì í wẹ* ọwọ́ wọn tí wọ́n bá fẹ́ jẹun.”+
3 Ó dá wọn lóhùn pé: “Kí ló dé tí ẹ̀ ń tẹ àṣẹ Ọlọ́run lójú torí àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ yín?+ 4 Bí àpẹẹrẹ, Ọlọ́run sọ pé, ‘Bọlá fún bàbá rẹ àti ìyá rẹ’+ àti pé, ‘Kí ẹ pa ẹni tó bá sọ̀rọ̀ òdì sí* bàbá tàbí ìyá rẹ̀.’+ 5 Àmọ́ ẹ sọ pé, ‘Ẹnikẹ́ni tó bá sọ fún bàbá tàbí ìyá rẹ̀ pé: “Ẹ̀bùn tí mo yà sí mímọ́ fún Ọlọ́run ni ohunkóhun tí mo ní tó lè ṣe yín láǹfààní,”+ 6 kò yẹ kó bọlá fún bàbá rẹ̀ rárá.’ Ẹ ti wá sọ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run di èyí tí kò lẹ́sẹ̀ nílẹ̀ nítorí àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ yín.+ 7 Ẹ̀yin alágàbàgebè, bí Àìsáyà ṣe sọ tẹ́lẹ̀ nípa yín ló rí gẹ́lẹ́, nígbà tó sọ pé:+ 8 ‘Àwọn èèyàn yìí ń fi ètè wọn bọlá fún mi, àmọ́ ọkàn wọn jìnnà gan-an sí mi. 9 Lásán ni wọ́n ń jọ́sìn mi, torí pé àṣẹ èèyàn ni ẹ̀kọ́ tí wọ́n fi ń kọ́ni.’”+ 10 Ó wá pe àwọn èrò náà sún mọ́ tòsí, ó sì sọ fún wọn pé: “Ẹ fetí sílẹ̀, kó sì yé yín:+ 11 Ohun tó ń wọ ẹnu èèyàn kọ́ ló ń sọ èèyàn di aláìmọ́, àmọ́ ohun tó ń ti ẹnu rẹ̀ jáde ló ń sọ ọ́ di aláìmọ́.”+
12 Àwọn ọmọ ẹ̀yìn sọ fún un pé: “Ǹjẹ́ o mọ̀ pé àwọn Farisí kọsẹ̀ nígbà tí wọ́n gbọ́ ohun tí o sọ?”+ 13 Ó fèsì pé: “Gbogbo ohun tí Baba mi ọ̀run kò gbìn la máa fà tu. 14 Ẹ fi wọ́n sílẹ̀. Afọ́jú tó ń fini mọ̀nà ni wọ́n. Tí afọ́jú bá wá ń fi afọ́jú mọ̀nà, inú kòtò ni àwọn méjèèjì máa já sí.”+ 15 Pétérù sọ pé: “La àpèjúwe náà yé wa.” 16 Ló bá sọ pé: “Ṣé kò tíì yé ẹ̀yin náà ni?+ 17 Ṣé ẹ ò mọ̀ pé ohunkóhun tó bá wọ ẹnu máa ń gba inú ikùn, tí a sì máa yà á jáde sínú kòtò ẹ̀gbin? 18 Àmọ́ ohunkóhun tó bá ń ti ẹnu jáde, inú ọkàn ló ti ń wá, àwọn nǹkan yẹn ló sì ń sọ èèyàn di aláìmọ́.+ 19 Bí àpẹẹrẹ, inú ọkàn ni àwọn èrò burúkú ti ń wá,+ irú bí: ìpànìyàn, àgbèrè, ìṣekúṣe,* olè jíjà, ìjẹ́rìí èké, ọ̀rọ̀ òdì. 20 Àwọn nǹkan yìí ló ń sọ èèyàn di aláìmọ́; àmọ́ èèyàn ò lè di aláìmọ́ tó bá jẹun láìwẹ* ọwọ́.”
21 Jésù kúrò níbẹ̀, ó lọ sí agbègbè Tírè àti Sídónì.+ 22 Wò ó! obìnrin ará Foníṣíà kan láti agbègbè yẹn wá, ó sì ń ké jáde pé: “Ṣàánú mi, Olúwa, Ọmọ Dáfídì. Ẹ̀mí èṣù ń yọ ọmọbìnrin mi lẹ́nu gidigidi.”+ 23 Àmọ́ kò dá a lóhùn rárá. Torí náà, àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ wá, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í rọ̀ ọ́ pé: “Ní kó máa lọ, torí kò yéé ké tẹ̀ lé wa.” 24 Ó fèsì pé: “A kò rán mi sí ẹnikẹ́ni àfi àwọn àgùntàn ilé Ísírẹ́lì tó sọ nù.”+ 25 Àmọ́ obìnrin náà wá tẹrí ba* fún un, ó sì ń sọ pé: “Olúwa, ràn mí lọ́wọ́!” 26 Ó fèsì pé: “Kò tọ́ ká mú búrẹ́dì àwọn ọmọ, ká sì jù ú sí àwọn ajá kéékèèké.” 27 Obìnrin náà sọ pé: “Bẹ́ẹ̀ ni, Olúwa, àmọ́ ká sòótọ́, àwọn ajá kéékèèké máa ń jẹ lára èérún tó ń já bọ́ látorí tábìlì àwọn ọ̀gá wọn.”+ 28 Jésù wá dá a lóhùn pé: “Ìwọ obìnrin yìí, ìgbàgbọ́ rẹ lágbára gan-an; kó ṣẹlẹ̀ sí ọ bí o ṣe fẹ́.” Ara ọmọbìnrin rẹ̀ sì yá láti wákàtí yẹn lọ.
29 Jésù kúrò níbẹ̀, ó wá lọ sí tòsí Òkun Gálílì,+ ó lọ sórí òkè, ó sì jókòó síbẹ̀. 30 Lẹ́yìn náà, èrò rẹpẹtẹ wá bá a, wọ́n mú àwọn èèyàn tó yarọ wá, àwọn aláàbọ̀ ara, afọ́jú, àwọn tí kò lè sọ̀rọ̀ àti ọ̀pọ̀ àwọn míì, wọ́n tẹ́ wọn síbi ẹsẹ̀ rẹ̀, ó sì wò wọ́n sàn.+ 31 Ẹnu ya àwọn èrò náà bí wọ́n ṣe rí i tí àwọn tí kò lè sọ̀rọ̀ ń sọ̀rọ̀, tí ara àwọn aláàbọ̀ ara ń yá, tí àwọn arọ ń rìn, tí àwọn afọ́jú sì ń ríran, wọ́n sì yin Ọlọ́run Ísírẹ́lì lógo.+
32 Àmọ́ Jésù pe àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ sọ́dọ̀, ó sì sọ pé: “Àánú àwọn èèyàn yìí ń ṣe mí,+ torí ọjọ́ kẹta nìyí tí wọ́n ti wà lọ́dọ̀ mi, tí wọn ò sì ní ohunkóhun tí wọ́n máa jẹ. Mi ò fẹ́ kí wọ́n lọ láìjẹun,* torí kí okun wọn má bàa tán lójú ọ̀nà.”+ 33 Ṣùgbọ́n àwọn ọmọ ẹ̀yìn sọ fún un pé: “Ibo la ti máa rí oúnjẹ tó máa tó bọ́ adúrú èrò yìí ní àdádó yìí?”+ 34 Jésù wá sọ fún wọn pé: “Búrẹ́dì mélòó lẹ ní?” Wọ́n sọ pé: “Méje àti ẹja wẹ́wẹ́ díẹ̀.” 35 Torí náà, lẹ́yìn tó sọ fún àwọn èrò náà pé kí wọ́n jókòó sílẹ̀,* 36 ó mú búrẹ́dì méje àti àwọn ẹja náà, lẹ́yìn tó sì dúpẹ́, ó bù ú, ó wá bẹ̀rẹ̀ sí í fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn, àwọn ọmọ ẹ̀yìn sì fún àwọn èrò náà.+ 37 Gbogbo wọn jẹ, wọ́n yó, ohun tó ṣẹ́ kù tí wọ́n kó jọ sì kún apẹ̀rẹ̀ ńlá* méje.+ 38 Ẹgbẹ̀rún mẹ́rin (4,000) ọkùnrin làwọn tó jẹ pẹ̀lú àwọn obìnrin àti àwọn ọmọdé. 39 Níkẹyìn, lẹ́yìn tó ní kí àwọn èrò náà máa lọ, ó wọ ọkọ̀ ojú omi, ó sì wá sí agbègbè Mágádánì.+
16 Àwọn Farisí àti àwọn Sadusí wá bá a, wọ́n ní kó fi àmì kan han àwọn láti ọ̀run, kí wọ́n lè dá an wò.+ 2 Ó dá wọn lóhùn pé: “Tó bá di ìrọ̀lẹ́, ẹ máa ń sọ pé, ‘Ojú ọjọ́ máa dáa, torí ojú ọ̀run pọ́n bí iná,’ 3 tó bá sì di àárọ̀, ẹ máa ń sọ pé ‘Ojú ọjọ́ máa tutù, òjò sì máa rọ̀ lónìí, torí ojú ọ̀run pọ́n bí iná, àmọ́ ó ṣú dùdù.’ Ẹ mọ bí wọ́n ṣe ń túmọ̀ ojú ọjọ́, àmọ́ ẹ ò lè túmọ̀ àwọn àmì àkókò. 4 Ìran burúkú àti alágbèrè* kò yéé wá àmì, àmọ́ a ò ní fún un ní àmì kankan+ àfi àmì Jónà.”+ Ló bá kúrò níbẹ̀, ó sì fi wọ́n sílẹ̀.
5 Àwọn ọmọ ẹ̀yìn sọdá sí òdìkejì, wọn ò sì rántí mú búrẹ́dì dání.+ 6 Jésù sọ fún wọn pé: “Ẹ la ojú yín sílẹ̀, kí ẹ sì ṣọ́ra fún ìwúkàrà àwọn Farisí àti àwọn Sadusí.”+ 7 Wọ́n wá bẹ̀rẹ̀ sí í rò ó láàárín ara wọn pé: “A ò mú búrẹ́dì kankan dání.” 8 Jésù mọ èyí, ó wá sọ pé: “Kí ló dé tí ẹ̀ ń sọ láàárín ara yín pé ẹ ò ní búrẹ́dì, ẹ̀yin tí ìgbàgbọ́ yín kéré? 9 Ṣé ọ̀rọ̀ yẹn ò tíì yé yín ni, àbí ẹ ò rántí búrẹ́dì márùn-ún tí mo fi bọ́ ẹgbẹ̀rún márùn-ún (5,000) àti iye apẹ̀rẹ̀ tí ẹ kó jọ?+ 10 Àbí búrẹ́dì méje tí mo fi bọ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́rin (4,000) àti iye apẹ̀rẹ̀ ńlá* tí ẹ kó jọ?+ 11 Kí nìdí tí kò fi yé yín pé ọ̀rọ̀ búrẹ́dì kọ́ ni mò ń bá yín sọ? Àmọ́, ẹ ṣọ́ra fún ìwúkàrà àwọn Farisí àti àwọn Sadusí.”+ 12 Ìgbà yẹn ló wá yé wọn pé kì í ṣe ìwúkàrà búrẹ́dì ló ní kí wọ́n ṣọ́ra fún, ẹ̀kọ́ àwọn Farisí àti àwọn Sadusí ni.
13 Nígbà tó dé agbègbè Kesaríà ti Fílípì, Jésù bi àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Ta ni àwọn èèyàn ń sọ pé Ọmọ èèyàn jẹ́?”+ 14 Wọ́n sọ pé: “Àwọn kan sọ pé Jòhánù Arinibọmi,+ àwọn míì ń sọ pé Èlíjà,+ àwọn míì sì ń sọ pé Jeremáyà tàbí ọ̀kan lára àwọn wòlíì.” 15 Ó wá bi wọ́n pé: “Ẹ̀yin ńkọ́, ta lẹ sọ pé mo jẹ́?” 16 Símónì Pétérù dáhùn pé: “Ìwọ ni Kristi náà,+ Ọmọ Ọlọ́run alààyè.”+ 17 Jésù sọ fún un pé: “Aláyọ̀ ni ọ́, Símónì ọmọ Jónà, torí pé ẹran ara àti ẹ̀jẹ̀* kọ́ ló ṣí i payá fún ọ, Baba mi tó wà lọ́run ni.+ 18 Bákan náà, mò ń sọ fún ọ pé: Ìwọ ni Pétérù,+ orí àpáta yìí+ sì ni màá kọ́ ìjọ mi sí, àwọn ibodè Isà Òkú* kò sì ní borí rẹ̀. 19 Màá fún ọ ní àwọn kọ́kọ́rọ́ Ìjọba ọ̀run, ohunkóhun tí o bá dè ní ayé máa jẹ́ ohun tí a ti dè ní ọ̀run, ohunkóhun tí o bá sì tú ní ayé máa jẹ́ ohun tí a ti tú ní ọ̀run.” 20 Ó wá kìlọ̀ gidigidi fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn pé kí wọ́n má sọ fún ẹnikẹ́ni pé òun ni Kristi náà.+
21 Látìgbà yẹn lọ, Jésù bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàlàyé fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé òun gbọ́dọ̀ lọ sí Jerúsálẹ́mù, kí òun jìyà tó pọ̀ lọ́wọ́ àwọn àgbààgbà, àwọn olórí àlùfáà àti àwọn akọ̀wé òfin, kí wọ́n sì pa òun, kí a sì jí òun dìde ní ọjọ́ kẹta.+ 22 Ni Pétérù bá mú un lọ sí ẹ̀gbẹ́ kan, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í bá a wí, ó sọ pé: “Ṣàánú ara rẹ, Olúwa; èyí ò ní ṣẹlẹ̀ sí ọ rárá.”+ 23 Àmọ́ ó yíjú pa dà, ó sì sọ fún Pétérù pé: “Dẹ̀yìn lẹ́yìn mi,* Sátánì! Ohun ìkọ̀sẹ̀ lo jẹ́ fún mi, torí èrò èèyàn lò ń rò, kì í ṣe ti Ọlọ́run.”+
24 Jésù wá sọ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Tí ẹnikẹ́ni bá fẹ́ máa tẹ̀ lé mi, kó sẹ́ ara rẹ̀, kó gbé òpó igi oró* rẹ̀, kó sì máa tẹ̀ lé mi.+ 25 Torí ẹnikẹ́ni tó bá fẹ́ gba ẹ̀mí* rẹ̀ là máa pàdánù rẹ̀, àmọ́ ẹnikẹ́ni tó bá pàdánù ẹ̀mí* rẹ̀ nítorí mi máa rí i.+ 26 Lóòótọ́, àǹfààní wo ni èèyàn máa rí tó bá jèrè gbogbo ayé àmọ́ tó pàdánù ẹ̀mí* rẹ̀?+ Àbí kí ni èèyàn máa fi dípò ẹ̀mí* rẹ̀?+ 27 Torí Ọmọ èèyàn máa wá nínú ògo Baba rẹ̀ pẹ̀lú àwọn áńgẹ́lì rẹ̀, ó máa wá san èrè fún kálukú gẹ́gẹ́ bí ìwà rẹ̀.+ 28 Lóòótọ́ ni mo sọ fún yín pé àwọn kan wà lára àwọn tó dúró síbí yìí tí kò ní tọ́ ikú wò rárá títí wọ́n á fi kọ́kọ́ rí Ọmọ èèyàn tó ń bọ̀ nínú Ìjọba rẹ̀.”+
17 Ọjọ́ mẹ́fà lẹ́yìn náà, Jésù mú Pétérù, Jémíìsì àti Jòhánù arákùnrin rẹ̀ dání lọ sí orí òkè kan tó ga fíofío láwọn nìkan.+ 2 A sì yí i pa dà di ológo níwájú wọn; ojú rẹ̀ tàn bí oòrùn, aṣọ àwọ̀lékè rẹ̀ sì tàn yòò* bí ìmọ́lẹ̀.+ 3 Wò ó! Mósè àti Èlíjà fara hàn wọ́n níbẹ̀, wọ́n ń bá a sọ̀rọ̀. 4 Pétérù wá sọ fún Jésù pé: “Olúwa, ó dáa bí a ṣe wà níbí. Tí o bá fẹ́, màá pa àgọ́ mẹ́ta síbí, ọ̀kan fún ọ, ọ̀kan fún Mósè àti ọ̀kan fún Èlíjà.” 5 Bí wọ́n ṣe ń sọ̀rọ̀ lọ́wọ́, wò ó! ìkùukùu* tó mọ́lẹ̀ yòò ṣíji bò wọ́n, sì wò ó! ohùn kan dún látinú ìkùukùu náà pé: “Èyí ni Ọmọ mi, àyànfẹ́, ẹni tí mo ti tẹ́wọ́ gbà.+ Ẹ fetí sí i.”+ 6 Nígbà tí wọ́n gbọ́ èyí, àwọn ọmọ ẹ̀yìn náà dojú bolẹ̀, ẹ̀rù sì bà wọ́n gidigidi. 7 Jésù wá sún mọ́ wọn, ó fọwọ́ kàn wọ́n, ó sì sọ pé: “Ẹ dìde. Ẹ má bẹ̀rù.” 8 Nígbà tí wọ́n gbójú sókè, wọn ò rí ẹnì kankan àfi Jésù nìkan. 9 Bí wọ́n ṣe ń sọ̀ kalẹ̀ látorí òkè náà, Jésù pàṣẹ fún wọn pé: “Ẹ má sọ ìran náà fún ẹnikẹ́ni títí a fi máa jí Ọmọ èèyàn dìde.”+
10 Àmọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn bi í pé: “Kí ló wá dé tí àwọn akọ̀wé òfin fi ń sọ pé Èlíjà gbọ́dọ̀ kọ́kọ́ wá?”+ 11 Ó fèsì pé: “Èlíjà ń bọ̀ lóòótọ́, ó sì máa mú kí gbogbo nǹkan pa dà sí bó ṣe yẹ.+ 12 Àmọ́ mò ń sọ fún yín pé Èlíjà ti wá, wọn ò sì dá a mọ̀, àmọ́ wọ́n ṣe ohun tó wù wọ́n sí i.+ Lọ́nà kan náà, Ọmọ èèyàn máa jìyà lọ́wọ́ wọn.”+ 13 Ìgbà yẹn ni àwọn ọmọ ẹ̀yìn fòye mọ̀ pé ọ̀rọ̀ Jòhánù Arinibọmi ló ń bá àwọn sọ.
14 Nígbà tí wọ́n dé ọ̀dọ̀ àwọn èrò,+ ọkùnrin kan wá bá a, ó kúnlẹ̀ fún un, ó sì sọ pé: 15 “Olúwa, ṣàánú ọmọkùnrin mi, torí ó ní wárápá, ara rẹ̀ ò sì yá. Ó máa ń ṣubú sínú iná àti sínú omi lọ́pọ̀ ìgbà.+ 16 Mo mú un wá sọ́dọ̀ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ, àmọ́ wọn ò lè wò ó sàn.” 17 Jésù fèsì pé: “Ìran aláìnígbàgbọ́ àti oníbékebèke,+ títí dìgbà wo ni màá fi wà pẹ̀lú yín? Títí dìgbà wo ni màá fi máa fara dà á fún yín? Ẹ mú un wá sọ́dọ̀ mi níbí.” 18 Jésù wá bá ẹ̀mí èṣù náà wí, ó sì jáde kúrò nínú ọmọkùnrin náà, ara ọmọ náà sì yá láti wákàtí yẹn.+ 19 Àwọn ọmọ ẹ̀yìn wá bá Jésù lóun nìkan, wọ́n sì sọ pé: “Kí ló dé tí a ò fi lè lé e jáde?” 20 Ó sọ fún wọn pé: “Torí ìgbàgbọ́ yín kéré ni. Lóòótọ́ ni mo sọ fún yín, tí ẹ bá ní ìgbàgbọ́ tó rí bíi hóró músítádì, ẹ máa sọ fún òkè yìí pé, ‘Kúrò níbí lọ sí ọ̀hún,’ ó sì máa lọ, kò sì sí ohun tí ẹ ò ní lè ṣe.”+ 21* ——
22 Ìgbà tí wọ́n kóra jọ sí Gálílì ni Jésù sọ fún wọn pé: “A máa fi Ọmọ èèyàn lé àwọn èèyàn lọ́wọ́,+ 23 wọ́n máa pa á, a sì máa jí i dìde ní ọjọ́ kẹta.”+ Inú wọn sì bà jẹ́ gidigidi.
24 Lẹ́yìn tí wọ́n dé Kápánáúmù, àwọn ọkùnrin tó ń gba dírákímà méjì* fún owó orí wá bá Pétérù, wọ́n sì sọ pé: “Ṣé olùkọ́ yín kì í san dírákímà méjì fún owó orí ni?”+ 25 Ó sọ pé: “Bẹ́ẹ̀ ni.” Àmọ́ nígbà tó wọnú ilé, Jésù ṣáájú rẹ̀ sọ̀rọ̀, ó bi í pé: “Kí lèrò rẹ, Símónì? Ọwọ́ ta ni àwọn ọba ayé ti ń gba owó ibodè tàbí owó orí? Ṣé ọwọ́ àwọn ọmọ wọn ni àbí ọwọ́ àwọn àjèjì?” 26 Nígbà tó sọ pé: “Ọwọ́ àwọn àjèjì ni,” Jésù sọ fún un pé: “Tó bá rí bẹ́ẹ̀, á jẹ́ pé àwọn ọmọ kì í san owó orí. 27 Àmọ́ ká má bàa mú wọn kọsẹ̀,+ lọ sí òkun, ju ìwọ̀ ẹja kan, kí o sì mú ẹja tó bá kọ́kọ́ jáde, tí o bá la ẹnu rẹ̀, wàá rí ẹyọ owó fàdákà kan.* Mú un, kí o sì fún wọn, kó jẹ́ tèmi àti tìrẹ.”
18 Ní wákàtí yẹn, àwọn ọmọ ẹ̀yìn wá sí tòsí Jésù, wọ́n sì bi í pé: “Ní tòótọ́, ta ló tóbi jù lọ nínú Ìjọba ọ̀run?”+ 2 Torí náà, ó pe ọmọ kékeré kan wá sọ́dọ̀ rẹ̀, ó mú un dúró ní àárín wọn, 3 ó sì sọ pé: “Lóòótọ́ ni mo sọ fún yín, láìjẹ́ pé ẹ yí pa dà,* kí ẹ sì dà bí àwọn ọmọdé,+ ó dájú pé ẹ ò ní wọ Ìjọba ọ̀run.+ 4 Torí náà, ẹnikẹ́ni tó bá rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀ bí ọmọ kékeré yìí ni ẹni tó tóbi jù lọ nínú Ìjọba ọ̀run;+ 5 ẹnikẹ́ni tó bá sì gba irú ọmọ kékeré bẹ́ẹ̀ nítorí orúkọ mi gba èmi náà. 6 Àmọ́ ẹnikẹ́ni tó bá mú ọ̀kan nínú àwọn ẹni kékeré yìí tó ní ìgbàgbọ́ nínú mi kọsẹ̀, ó sàn ká so ọlọ mọ́ ọn lọ́rùn, irú èyí tí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ máa ń yí, ká sì jù ú sínú agbami òkun, kó sì rì.+
7 “Ó mà ṣe fún ayé o, nítorí àwọn ohun ìkọ̀sẹ̀! Lóòótọ́, ó di dandan kí àwọn ohun ìkọ̀sẹ̀ wá, àmọ́ ó mà ṣe o, fún ẹni tí ohun ìkọ̀sẹ̀ náà tipasẹ̀ rẹ̀ wá! 8 Torí náà, tí ọwọ́ rẹ tàbí ẹsẹ̀ rẹ bá ń mú ọ kọsẹ̀, gé e, kí o sì sọ ọ́ nù kúrò lọ́dọ̀ rẹ.+ Ó sàn fún ọ láti jogún ìyè ní aláàbọ̀ ara tàbí ní arọ ju kí a jù ọ́ sínú iná àìnípẹ̀kun+ pẹ̀lú ọwọ́ méjèèjì tàbí ẹsẹ̀ méjèèjì. 9 Bákan náà, tí ojú rẹ bá ń mú ọ kọsẹ̀, yọ ọ́, kí o sì sọ ọ́ nù kúrò lọ́dọ̀ rẹ. Ó sàn fún ọ láti jogún ìyè ní olójú kan ju kí a jù ọ́ sínú Gẹ̀hẹ́nà* oníná+ pẹ̀lú ojú méjèèjì. 10 Ẹ rí i pé ẹ ò kẹ́gàn ọ̀kan nínú àwọn ẹni kékeré yìí, torí mò ń sọ fún yín pé ìgbà gbogbo ni àwọn áńgẹ́lì wọn ní ọ̀run máa ń wo ojú Baba mi tó wà ní ọ̀run.+ 11* ——
12 “Kí lèrò yín? Tí ọkùnrin kan bá ní ọgọ́rùn-ún (100) àgùntàn, tí ọ̀kan nínú wọn sì sọ nù,+ ṣebí ó máa fi mọ́kàndínlọ́gọ́rùn-ún (99) yòókù sílẹ̀ lórí òkè ni, kó sì bẹ̀rẹ̀ sí í wá èyí tó sọ nù?+ 13 Tó bá sì rí i, mò ń sọ fún yín, ó dájú pé ó máa yọ̀ gidigidi torí rẹ̀ ju mọ́kàndínlọ́gọ́rùn-ún (99) tí kò tíì sọ nù. 14 Bákan náà, kò wu Baba mi* tó wà ní ọ̀run pé kí ọ̀kan péré nínú àwọn ẹni kékeré yìí ṣègbé.+
15 “Bákan náà, tí arákùnrin rẹ bá ṣẹ̀, lọ sọ ẹ̀bi rẹ̀ fún un* láàárín ìwọ àti òun nìkan.+ Tó bá fetí sí ọ, o ti jèrè arákùnrin rẹ.+ 16 Àmọ́ tí kò bá fetí sí ọ, mú ẹnì kan tàbí méjì dání, kó lè jẹ́ pé nípa ẹ̀rí* ẹni méjì tàbí mẹ́ta, a ó fìdí gbogbo ọ̀rọ̀ múlẹ̀.+ 17 Tí kò bá fetí sí wọn, sọ fún ìjọ. Tí kò bá fetí sí ìjọ pàápàá, bí èèyàn àwọn orílẹ̀-èdè+ àti agbowó orí+ ni kó rí sí ọ gẹ́lẹ́.
18 “Lóòótọ́ ni mo sọ fún yín, ohunkóhun tí ẹ bá dè ní ayé máa jẹ́ ohun tí a ti dè ní ọ̀run, ohunkóhun tí ẹ bá sì tú ní ayé máa jẹ́ ohun tí a ti tú ní ọ̀run. 19 Mo tún sọ fún yín lóòótọ́ pé, tí ẹni méjì nínú yín ní ayé bá fohùn ṣọ̀kan lórí ohunkóhun tó ṣe pàtàkì tí wọ́n máa béèrè, ó máa rí bẹ́ẹ̀ fún wọn nítorí Baba mi tó wà ní ọ̀run.+ 20 Torí ibi tí ẹni méjì tàbí mẹ́ta bá kóra jọ sí ní orúkọ mi,+ mo wà níbẹ̀ láàárín wọn.”
21 Pétérù wá, ó sì sọ fún un pé: “Olúwa, ìgbà mélòó ni arákùnrin mi máa ṣẹ̀ mí, tí màá sì dárí jì í? Ṣé kó tó ìgbà méje?” 22 Jésù sọ fún un pé: “Mò ń sọ fún ọ pé, kì í ṣe ìgbà méje, àmọ́ kó tó ìgbà àádọ́rin lé méje (77).+
23 “Ìdí nìyẹn tí a ṣe lè fi Ìjọba ọ̀run wé ọba kan tó fẹ́ yanjú ọ̀rọ̀ owó pẹ̀lú àwọn ẹrú rẹ̀. 24 Nígbà tó bẹ̀rẹ̀ sí í yanjú rẹ̀, wọ́n mú ọkùnrin kan wọlé tó jẹ ẹ́ ní gbèsè ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá (10,000) tálẹ́ńtì.* 25 Àmọ́ torí pé kò ní ohun tó máa fi san án pa dà, ọ̀gá rẹ̀ pàṣẹ pé kí wọ́n ta òun, ìyàwó rẹ̀, àwọn ọmọ rẹ̀ àti gbogbo ohun tó ní, kí wọ́n sì fi san gbèsè náà.+ 26 Ni ẹrú náà bá wólẹ̀, ó sì forí balẹ̀* fún un, ó sọ pé, ‘Ní sùúrù fún mi, màá sì san gbogbo rẹ̀ pa dà fún ọ.’ 27 Àánú ẹrú náà wá ṣe ọ̀gá rẹ̀, ó fi sílẹ̀, ó sì fagi lé gbèsè rẹ̀.+ 28 Àmọ́ ẹrú yẹn jáde lọ, ó sì rí ọ̀kan lára àwọn tí wọ́n jọ jẹ́ ẹrú, tó jẹ ẹ́ ní gbèsè ọgọ́rùn-ún (100) owó dínárì,* ó rá a mú, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í fún un lọ́rùn, ó sọ pé, ‘San gbogbo gbèsè tí o jẹ pa dà.’ 29 Torí náà, ẹrú ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ wólẹ̀, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í bẹ̀ ẹ́, ó sọ pé, ‘Ní sùúrù fún mi, màá sì san án pa dà fún ọ.’ 30 Àmọ́ kò gbà, ló bá ní kí wọ́n jù ú sẹ́wọ̀n títí ó fi máa san gbèsè tó jẹ pa dà. 31 Nígbà tí àwọn tí wọ́n jọ jẹ́ ẹrú rí ohun tó ṣẹlẹ̀, inú wọn bà jẹ́ gan-an, wọ́n sì lọ ròyìn gbogbo ohun tó ṣẹlẹ̀ fún ọ̀gá wọn. 32 Ọ̀gá rẹ̀ wá ránṣẹ́ pè é, ó sì sọ fún un pé: ‘Ẹrú burúkú, mo fagi lé gbogbo gbèsè yẹn fún ọ nígbà tí o bẹ̀ mí. 33 Ṣé kò yẹ kí ìwọ náà ṣàánú ẹrú ẹlẹgbẹ́ rẹ bí mo ṣe ṣàánú rẹ?’+ 34 Èyí múnú bí ọ̀gá rẹ̀ gidigidi, ló bá fà á lé àwọn tó ń ṣọ́ àwọn ẹlẹ́wọ̀n lọ́wọ́, títí ó fi máa san gbogbo gbèsè tó jẹ pa dà. 35 Bẹ́ẹ̀ náà ni Baba mi ọ̀run máa ṣe sí yín+ tí kálukú yín kò bá dárí ji arákùnrin rẹ̀ látọkàn wá.”+
19 Nígbà tí Jésù sọ àwọn ọ̀rọ̀ yìí tán, ó kúrò ní Gálílì, ó sì wá sí ààlà ilẹ̀ Jùdíà ní òdìkejì Jọ́dánì.+ 2 Èrò rẹpẹtẹ tún tẹ̀ lé e, ó sì wò wọ́n sàn níbẹ̀.
3 Àwọn Farisí wá bá a, wọ́n fẹ́ dán an wò, wọ́n sì bi í pé: “Ṣé ó bófin mu fún ọkùnrin láti kọ ìyàwó rẹ̀ sílẹ̀ lórí gbogbo ẹ̀sùn?”+ 4 Ó dá wọn lóhùn pé: “Ṣé ẹ ò kà á pé ẹni tó dá wọn ní ìbẹ̀rẹ̀ dá wọn ní akọ àti abo,+ 5 ó sì sọ pé, ‘Torí èyí, ọkùnrin á fi bàbá rẹ̀ àti ìyá rẹ̀ sílẹ̀, á sì fà mọ́ ìyàwó rẹ̀, àwọn méjèèjì á sì di ara kan’?+ 6 Tó fi jẹ́ pé wọn kì í ṣe méjì mọ́, àmọ́ wọ́n jẹ́ ara kan. Torí náà, ohun tí Ọlọ́run ti so pọ̀, kí èèyàn kankan má ṣe yà á.”+ 7 Wọ́n sọ fún un pé: “Kí ló wá dé tí Mósè fi sọ pé ká fún un ní ìwé ẹ̀rí láti lé e lọ, ká sì kọ̀ ọ́ sílẹ̀?”+ 8 Ó sọ fún wọn pé: “Torí pé ọkàn yín le ni Mósè ṣe yọ̀ǹda fún yín láti kọ ìyàwó yín sílẹ̀,+ àmọ́ kò rí bẹ́ẹ̀ láti ìbẹ̀rẹ̀.+ 9 Mò ń sọ fún yín pé ẹnikẹ́ni tó bá kọ ìyàwó rẹ̀ sílẹ̀, àfi tó bá jẹ́ torí ìṣekúṣe,* tó sì fẹ́ ẹlòmíì ti ṣe àgbèrè.”+
10 Àwọn ọmọ ẹ̀yìn sọ fún un pé: “Tó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀ ni ọ̀rọ̀ ọkùnrin àti ìyàwó rẹ̀ rí, ó sàn kéèyàn má tiẹ̀ níyàwó.” 11 Ó sọ fún wọn pé: “Kì í ṣe gbogbo èèyàn ló ń wá àyè láti ṣe bẹ́ẹ̀, àfi àwọn tó ní ẹ̀bùn rẹ̀.+ 12 Torí àwọn kan wà tí a bí ní ìwẹ̀fà, àwọn ìwẹ̀fà kan wà tí àwọn èèyàn sọ di ìwẹ̀fà, àwọn ìwẹ̀fà kan sì wà tí wọ́n ti sọ ara wọn di ìwẹ̀fà nítorí Ìjọba ọ̀run. Kí ẹni tó bá lè wá àyè fún un wá àyè fún un.”+
13 Wọ́n mú àwọn ọmọdé wá sọ́dọ̀ rẹ̀, kó lè gbé ọwọ́ rẹ̀ lé wọn, kó sì gbàdúrà, àmọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn bá wọn wí.+ 14 Ṣùgbọ́n Jésù sọ pé: “Ẹ fi àwọn ọmọdé sílẹ̀, ẹ má sì dá wọn dúró láti wá sọ́dọ̀ mi, torí Ìjọba ọ̀run jẹ́ ti irú wọn.”+ 15 Ó gbé ọwọ́ rẹ̀ lé wọn, ó sì kúrò níbẹ̀.
16 Wò ó! ẹnì kan wá bá a, ó sì sọ pé: “Olùkọ́, ohun rere wo ni mo gbọ́dọ̀ ṣe kí n lè ní ìyè àìnípẹ̀kun?”+ 17 Ó sọ fún un pé: “Kí ló dé tí o fi ń bi mí nípa ohun rere? Ẹni rere kan ló wà.+ Àmọ́ o, tí o bá fẹ́ jogún ìyè, máa pa àwọn àṣẹ mọ́ nígbà gbogbo.”+ 18 Ó bi í pé: “Àwọn àṣẹ wo?” Jésù sọ pé: “O ò gbọ́dọ̀ pààyàn,+ o ò gbọ́dọ̀ ṣe àgbèrè,+ o ò gbọ́dọ̀ jalè,+ o ò gbọ́dọ̀ jẹ́rìí èké,+ 19 bọlá fún bàbá rẹ àti ìyá rẹ+ àti pé, kí o nífẹ̀ẹ́ ọmọnìkejì rẹ bí ara rẹ.”+ 20 Ọ̀dọ́kùnrin náà sọ fún un pé: “Mo ti ń ṣe gbogbo nǹkan yìí; kí ló kù tí mi ò tíì ṣe?” 21 Jésù sọ fún un pé: “Tí o bá fẹ́ jẹ́ pípé,* lọ ta àwọn ohun ìní rẹ, kí o fún àwọn aláìní, wàá sì ní ìṣúra ní ọ̀run;+ kí o wá máa tẹ̀ lé mi.”+ 22 Nígbà tí ọ̀dọ́kùnrin náà gbọ́ èyí, ó fi ìbànújẹ́ kúrò, torí ohun ìní rẹ̀ pọ̀.+ 23 Jésù wá sọ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Lóòótọ́ ni mo sọ fún yín pé, ó máa ṣòro fún ọlọ́rọ̀ láti wọ Ìjọba ọ̀run.+ 24 Mo tún ń sọ fún yín pé, ó rọrùn fún ràkúnmí láti gba ojú abẹ́rẹ́ kọjá ju fún ọlọ́rọ̀ láti wọ Ìjọba Ọlọ́run.”+
25 Nígbà tí àwọn ọmọ ẹ̀yìn gbọ́ ọ̀rọ̀ yẹn, ó yà wọ́n lẹ́nu gan-an, wọ́n sọ pé: “Ta ló máa wá lè rí ìgbàlà?”+ 26 Jésù bá tẹjú mọ́ wọn, ó sì sọ pé: “Lójú èèyàn, èyí kò ṣeé ṣe, àmọ́ ohun gbogbo ṣeé ṣe fún Ọlọ́run.”+
27 Ni Pétérù bá fèsì pé: “Wò ó! A ti fi ohun gbogbo sílẹ̀, a sì tẹ̀ lé ọ; kí ló máa wá jẹ́ tiwa?”+ 28 Jésù sọ fún wọn pé: “Lóòótọ́ ni mo sọ fún yín, nígbà àtúndá, tí Ọmọ èèyàn bá jókòó sórí ìtẹ́ ògo rẹ̀, ẹ̀yin tí ẹ ti tẹ̀ lé mi máa jókòó sórí ìtẹ́ méjìlá (12), ẹ sì máa ṣèdájọ́ ẹ̀yà méjìlá (12) Ísírẹ́lì.+ 29 Gbogbo ẹni tó bá sì ti fi àwọn ilé tàbí àwọn arákùnrin, àwọn arábìnrin, bàbá, ìyá, àwọn ọmọ tàbí àwọn ilẹ̀ sílẹ̀ nítorí orúkọ mi máa gba ìlọ́po ọgọ́rùn-ún (100), ó sì máa jogún ìyè àìnípẹ̀kun.+
30 “Àmọ́ ọ̀pọ̀ àwọn ẹni àkọ́kọ́ máa di ẹni ìkẹyìn, àwọn ẹni ìkẹyìn sì máa di ẹni àkọ́kọ́.+
20 “Torí Ìjọba ọ̀run dà bíi baálé ilé kan tó jáde lọ ní àárọ̀ kùtù láti gba àwọn òṣìṣẹ́ sínú ọgbà àjàrà rẹ̀.+ 2 Lẹ́yìn tó bá àwọn òṣìṣẹ́ náà ṣàdéhùn pé òun máa fún wọn ní owó dínárì* kan fún ọjọ́ kan, ó ní kí wọ́n lọ sínú ọgbà àjàrà òun. 3 Ó tún jáde ní nǹkan bíi wákàtí kẹta,* ó sì rí àwọn míì tí wọ́n dúró ní ibi ọjà, tí wọn ò ríṣẹ́ ṣe; 4 ó sọ fún wọn pé, ‘Ẹ̀yin náà, ẹ lọ sínú ọgbà àjàrà, màá sì fún yín ní ohunkóhun tó bá tọ́.’ 5 Torí náà, wọ́n lọ. Ó tún jáde ní nǹkan bíi wákàtí kẹfà* àti wákàtí kẹsàn-án,* ó sì ṣe ohun kan náà. 6 Níkẹyìn, ní nǹkan bíi wákàtí kọkànlá,* ó jáde lọ, ó sì rí àwọn míì tí wọ́n dúró, ó sọ fún wọn pé, ‘Kí ló dé tí ẹ dúró síbí látàárọ̀, tí ẹ ò ríṣẹ́ ṣe?’ 7 Wọ́n sọ fún un pé, ‘Torí kò sẹ́ni tó gbà wá síṣẹ́ ni.’ Ó sọ fún wọn pé, ‘Ẹ̀yin náà, ẹ lọ sínú ọgbà àjàrà.’
8 “Nígbà tó di ìrọ̀lẹ́, ẹni tó ni ọgbà àjàrà náà sọ fún ọkùnrin tó fi ṣe alábòójútó pé, ‘Pe àwọn òṣìṣẹ́, kí o sì san owó iṣẹ́ wọn fún wọn,+ bẹ̀rẹ̀ látorí àwọn tó dé kẹ́yìn títí dórí àwọn ẹni àkọ́kọ́.’ 9 Nígbà tí àwọn ọkùnrin tó dé ní wákàtí kọkànlá wá, ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn gba owó dínárì* kan. 10 Nígbà tí àwọn ẹni àkọ́kọ́ wá dé, wọ́n rò pé àwọn máa gbà jù bẹ́ẹ̀ lọ, àmọ́ owó dínárì* kan ni wọ́n san fún àwọn náà. 11 Nígbà tí wọ́n gbà á, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàròyé fún baálé ilé náà, 12 wọ́n sì sọ pé, ‘Iṣẹ́ wákàtí kan ni àwọn tó dé kẹ́yìn yìí ṣe; síbẹ̀ iye kan náà lo fún àwa tí a ṣiṣẹ́ kára látàárọ̀ nínú ooru tó mú gan-an!’ 13 Àmọ́ ó dá ọ̀kan nínú wọn lóhùn pé, ‘Ọ̀gbẹ́ni, mi ò hùwà àìtọ́ sí ọ. Àdéhùn owó dínárì* kan la jọ ṣe, àbí bẹ́ẹ̀ kọ́?+ 14 Gba ohun tó jẹ́ tìrẹ, kí o sì máa lọ. Iye tí mo fún ẹni tó dé kẹ́yìn yìí náà ni màá fún ọ. 15 Ṣé mi ò lẹ́tọ̀ọ́ láti fi àwọn nǹkan mi ṣe ohun tó wù mí ni? Àbí ṣé ojú rẹ ń ṣe ìlara* torí mo jẹ́ ẹni rere* ni?’+ 16 Lọ́nà yìí, àwọn ẹni ìkẹyìn máa di ẹni àkọ́kọ́, àwọn ẹni àkọ́kọ́ sì máa di ẹni ìkẹyìn.”+
17 Bí wọ́n ṣe ń gòkè lọ sí Jerúsálẹ́mù, Jésù pe àwọn ọmọ ẹ̀yìn méjìlá (12) náà sí ẹ̀gbẹ́ kan láwọn nìkan, ó sì sọ fún wọn lójú ọ̀nà pé:+ 18 “Ẹ wò ó! À ń gòkè lọ sí Jerúsálẹ́mù, wọ́n sì máa fa Ọmọ èèyàn lé àwọn olórí àlùfáà àti àwọn akọ̀wé òfin lọ́wọ́. Wọ́n máa dájọ́ ikú fún un,+ 19 wọ́n sì máa fà á lé àwọn èèyàn orílẹ̀-èdè lọ́wọ́ kí wọ́n lè fi ṣe yẹ̀yẹ́, kí wọ́n nà án, kí wọ́n sì kàn án mọ́gi;+ a sì máa jí i dìde ní ọjọ́ kẹta.”+
20 Ìyá àwọn ọmọ Sébédè+ pẹ̀lú àwọn ọmọ rẹ̀ wá bá a, obìnrin náà tẹrí ba* fún un, ó sì béèrè ohun kan lọ́wọ́ rẹ̀.+ 21 Ó sọ fún obìnrin náà pé: “Kí lo fẹ́?” Ó fèsì pé: “Pàṣẹ pé kí àwọn ọmọ mi méjèèjì yìí jókòó, ọ̀kan ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ àti ọ̀kan ní òsì rẹ, nínú Ìjọba rẹ.”+ 22 Jésù dáhùn pé: “Ẹ ò mọ ohun tí ẹ̀ ń béèrè. Ṣé ẹ lè mu ife tí mo máa tó mu?”+ Wọ́n sọ fún un pé: “A lè mu ún.” 23 Ó sọ fún wọn pé: “Ó dájú pé ẹ máa mu ife mi,+ àmọ́ èmi kọ́ ló máa sọ ẹni tó máa jókòó sí ọwọ́ ọ̀tún mi àti sí òsì mi, ṣùgbọ́n ó máa wà fún àwọn tí Baba mi ti ṣètò rẹ̀ fún.”+
24 Nígbà tí àwọn mẹ́wàá yòókù gbọ́ nípa rẹ̀, wọ́n bínú sí tẹ̀gbọ́n-tàbúrò náà.+ 25 Àmọ́ Jésù pè wọ́n sọ́dọ̀, ó sì sọ pé: “Ẹ mọ̀ pé àwọn alákòóso orílẹ̀-èdè máa ń jẹ ọ̀gá lé àwọn èèyàn lórí, àwọn èèyàn ńlá sì máa ń lo àṣẹ lórí wọn.+ 26 Kò gbọ́dọ̀ rí bẹ́ẹ̀ láàárín yín;+ àmọ́ ẹnikẹ́ni tó bá fẹ́ di ẹni ńlá láàárín yín gbọ́dọ̀ jẹ́ ìránṣẹ́ yín,+ 27 ẹnikẹ́ni tó bá sì fẹ́ jẹ́ ẹni àkọ́kọ́ láàárín yín gbọ́dọ̀ jẹ́ ẹrú yín.+ 28 Gẹ́gẹ́ bí Ọmọ èèyàn ò ṣe wá ká lè ṣe ìránṣẹ́ fún un, àmọ́ kó lè ṣe ìránṣẹ́,+ kó sì fi ẹ̀mí* rẹ̀ ṣe ìràpadà ní pàṣípààrọ̀ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn.”+
29 Bí wọ́n ṣe ń kúrò ní Jẹ́ríkò, èrò rẹpẹtẹ tẹ̀ lé e. 30 Wò ó! àwọn ọkùnrin afọ́jú méjì tí wọ́n jókòó sẹ́gbẹ̀ẹ́ ọ̀nà gbọ́ pé Jésù ń kọjá lọ, wọ́n kígbe pé: “Olúwa, ṣàánú wa, Ọmọ Dáfídì!”+ 31 Àmọ́ àwọn èrò náà bá wọn wí, wọ́n ní kí wọ́n dákẹ́; àmọ́ ṣe ni wọ́n tún ń kígbe sókè pé: “Olúwa, ṣàánú wa, Ọmọ Dáfídì!” 32 Torí náà, Jésù dúró, ó pè wọ́n, ó sì sọ pé: “Kí lẹ fẹ́ kí n ṣe fún yín?” 33 Wọ́n sọ fún un pé: “Olúwa, jẹ́ kí ojú wa là.” 34 Àánú wọn ṣe Jésù, ó sì fọwọ́ kan ojú wọn,+ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ wọ́n pa dà ríran, wọ́n sì tẹ̀ lé e.
21 Nígbà tí wọ́n sún mọ́ Jerúsálẹ́mù, tí wọ́n sì dé Bẹtifágè lórí Òkè Ólífì, Jésù rán ọmọ ẹ̀yìn méjì jáde,+ 2 ó sọ fún wọn pé: “Ẹ lọ sínú abúlé ọ̀ọ́kán yìí, gbàrà tí ẹ bá débẹ̀, ẹ máa rí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ kan tí wọ́n so àti ọmọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́* tó wà pẹ̀lú rẹ̀. Ẹ tú wọn, kí ẹ sì mú wọn wá fún mi. 3 Tí ẹnì kan bá bá yín sọ ohunkóhun, kí ẹ sọ pé, ‘Olúwa fẹ́ lò wọ́n.’ Ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ló máa fi wọ́n ránṣẹ́.”
4 Èyí ṣẹlẹ̀ kí ohun tí a sọ nípasẹ̀ wòlíì lè ṣẹ, ẹni tó sọ pé: 5 “Ẹ sọ fún ọmọbìnrin Síónì pé: ‘Wò ó! Ọba rẹ ń bọ̀ lọ́dọ̀ rẹ,+ oníwà tútù ni,+ ó sì gun kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, àní, ọmọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, ọmọ ẹran akẹ́rù.’”+
6 Àwọn ọmọ ẹ̀yìn wá lọ, wọ́n sì ṣe ohun tí Jésù ní kí wọ́n ṣe gẹ́lẹ́.+ 7 Wọ́n mú kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà àti ọmọ rẹ̀ wá, wọ́n tẹ́ aṣọ àwọ̀lékè wọn sórí wọn, ó sì jókòó sórí wọn.+ 8 Ọ̀pọ̀ nínú àwọn èrò náà tẹ́ aṣọ àwọ̀lékè wọn sí ojú ọ̀nà,+ àwọn míì ń gé àwọn ẹ̀ka igi, wọ́n sì ń tẹ́ wọn sí ojú ọ̀nà. 9 Bákan náà, àwọn èrò tó ń lọ níwájú rẹ̀ àti àwọn tó ń tẹ̀ lé e ń kígbe ṣáá pé: “A bẹ̀ ọ́, gba Ọmọ Dáfídì là!+ Ìbùkún ni fún ẹni tó ń bọ̀ ní orúkọ Jèhófà!*+ A bẹ̀ ọ́, gbà á là, ní ibi gíga lókè!”+
10 Nígbà tó wọ Jerúsálẹ́mù, ariwo sọ ní gbogbo ìlú náà, wọ́n ń sọ pé: “Ta nìyí?” 11 Àwọn èrò náà ń sọ ṣáá pé: “Jésù nìyí, wòlíì+ tó wá láti Násárẹ́tì ti Gálílì!”
12 Jésù wọnú tẹ́ńpìlì, ó lé gbogbo àwọn tó ń tajà àti àwọn tó ń rajà nínú tẹ́ńpìlì síta, ó sì dojú tábìlì àwọn tó ń pààrọ̀ owó dé àti bẹ́ǹṣì àwọn tó ń ta àdàbà.+ 13 Ó sọ fún wọn pé: “A ti kọ ọ́ pé, ‘A ó máa pe ilé mi ní ilé àdúrà,’+ àmọ́ ẹ̀ ń sọ ọ́ di ihò àwọn olè.”+ 14 Bákan náà, àwọn afọ́jú àti àwọn arọ wá sọ́dọ̀ rẹ̀ nínú tẹ́ńpìlì, ó sì wò wọ́n sàn.
15 Nígbà tí àwọn olórí àlùfáà àti àwọn akọ̀wé òfin rí àwọn ohun ìyanu tó ṣe àti àwọn ọmọkùnrin tó ń kígbe nínú tẹ́ńpìlì pé, “A bẹ̀ ọ́, gba Ọmọ Dáfídì là!”+ inú bí wọn gidigidi,+ 16 wọ́n sì sọ fún un pé: “Ṣé o gbọ́ ohun tí àwọn yìí ń sọ?” Jésù sọ fún wọn pé: “Bẹ́ẹ̀ ni. Ṣé ẹ ò kà á rí pé, ‘Láti ẹnu àwọn ọmọdé àti àwọn ọmọ jòjòló lo ti mú kí ìyìn jáde’?”+ 17 Ó wá fi wọ́n sílẹ̀, ó kúrò ní ìlú náà lọ sí Bẹ́tánì, ó sì sun ibẹ̀ mọ́jú.+
18 Nígbà tó ń pa dà sí ìlú náà ní àárọ̀ kùtù, ebi ń pa á.+ 19 Ó tajú kán rí igi ọ̀pọ̀tọ́ kan létí ọ̀nà, ó sì lọ sí ìdí rẹ̀, àmọ́ kò rí nǹkan kan lórí rẹ̀ àfi ewé,+ ó wá sọ fún un pé: “Kí èso kankan má so lórí rẹ mọ́ títí láé.”+ Igi ọ̀pọ̀tọ́ náà sì rọ lójú ẹsẹ̀. 20 Nígbà tí àwọn ọmọ ẹ̀yìn rí èyí, ó yà wọ́n lẹ́nu, wọ́n sì sọ pé: “Kí ló mú kí igi ọ̀pọ̀tọ́ náà rọ lójú ẹsẹ̀?”+ 21 Jésù fèsì pé: “Lóòótọ́ ni mo sọ fún yín, tí ẹ bá ní ìgbàgbọ́, tí ẹ ò sì ṣiyèméjì, ohun tí mo ṣe sí igi ọ̀pọ̀tọ́ náà nìkan kọ́ lẹ máa lè ṣe, àmọ́ tí ẹ bá sọ fún òkè yìí pé, ‘Dìde, wọnú òkun,’ ó máa ṣẹlẹ̀.+ 22 Gbogbo ohun tí ẹ bá sì béèrè nínú àdúrà, tí ẹ bá ní ìgbàgbọ́, ẹ máa rí i gbà.”+
23 Lẹ́yìn tó lọ sínú tẹ́ńpìlì, àwọn olórí àlùfáà àti àwọn àgbààgbà àwọn èèyàn náà wá sọ́dọ̀ rẹ̀ nígbà tó ń kọ́ni, wọ́n sì sọ pé: “Àṣẹ wo lo fi ń ṣe àwọn nǹkan yìí? Ta ló sì fún ọ ní àṣẹ yìí?”+ 24 Jésù dá wọn lóhùn pé: “Èmi náà á bi yín ní ohun kan, tí ẹ bá sọ fún mi, èmi náà á sọ àṣẹ tí mo fi ń ṣe àwọn nǹkan yìí fún yín: 25 Ìrìbọmi tí Jòhánù ṣe fún àwọn èèyàn, ibo ló ti wá? Ṣé láti ọ̀run ni àbí látọ̀dọ̀ èèyàn?”* Wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í rò ó láàárín ara wọn pé: “Tí a bá sọ pé, ‘Láti ọ̀run,’ ó máa sọ fún wa pé, ‘Kí ló wá dé tí ẹ ò gbà á+ gbọ́?’ 26 Àmọ́ tí a bá sọ pé, ‘Látọ̀dọ̀ èèyàn,’ ẹ̀rù àwọn èrò yìí ń bà wá, torí wòlíì ni gbogbo wọn ka Jòhánù sí.” 27 Torí náà, wọ́n dá Jésù lóhùn pé: “A ò mọ̀.” Ó wá sọ fún wọn pé: “Èmi náà ò ní sọ àṣẹ tí mo fi ń ṣe àwọn nǹkan yìí fún yín.
28 “Kí lèrò yín? Ọkùnrin kan ní ọmọ méjì. Ó lọ bá àkọ́kọ́, ó sọ pé, ‘Ọmọ, lọ ṣiṣẹ́ nínú ọgbà àjàrà lónìí.’ 29 Ọmọ náà fèsì pé, ‘Mi ò lọ,’ àmọ́ lẹ́yìn náà, ó pèrò dà, ó sì lọ. 30 Ó lọ bá ìkejì, ó sọ ohun kan náà fún un. Ọmọ náà sì fèsì pé, ‘Màá lọ Sà,’ àmọ́ kò lọ. 31 Èwo nínú àwọn méjèèjì ló ṣe ìfẹ́ bàbá rẹ̀?” Wọ́n sọ pé: “Èyí àkọ́kọ́.” Jésù sọ fún wọn pé: “Lóòótọ́ ni mo sọ fún yín pé, àwọn agbowó orí àti àwọn aṣẹ́wó máa ṣáájú yín lọ sínú Ìjọba Ọlọ́run. 32 Torí Jòhánù wá sọ́dọ̀ yín ní ọ̀nà òdodo, àmọ́ ẹ ò gbà á gbọ́. Ṣùgbọ́n àwọn agbowó orí àti àwọn aṣẹ́wó gbà á gbọ́,+ kódà nígbà tí ẹ rí èyí, ẹ ò pèrò dà lẹ́yìn náà kí ẹ lè gbà á gbọ́.
33 “Ẹ gbọ́ àpèjúwe míì: Ọkùnrin kan wà, ó ní ilẹ̀, ó gbin àjàrà, ó sì ṣe ọgbà yí i ká,+ ó gbẹ́ ibi tí wọ́n ti ń fún wáìnì sínú rẹ̀, ó sì kọ́ ilé gogoro kan;+ ó wá gbé e fún àwọn tó ń dáko, ó sì rin ìrìn àjò lọ sí ilẹ̀ òkèèrè.+ 34 Nígbà tó di àsìkò tí èso ń so, ó rán àwọn ẹrú rẹ̀ lọ sọ́dọ̀ àwọn tó ń dáko náà pé kí wọ́n gba àwọn èso rẹ̀ wá. 35 Àmọ́ àwọn tó ń dáko náà mú àwọn ẹrú rẹ̀, wọ́n lu ọ̀kan nílùkulù, wọ́n pa ìkejì, wọ́n sì sọ òmíràn lókùúta.+ 36 Ó tún rán àwọn ẹrú míì, tí wọ́n pọ̀ ju àwọn ti àkọ́kọ́ lọ, àmọ́ ohun kan náà ni wọ́n ṣe sí àwọn yìí.+ 37 Níkẹyìn, ó rán ọmọ rẹ̀ sí wọn, ó ní, ‘Wọ́n máa bọ̀wọ̀ fún ọmọ mi.’ 38 Nígbà tí wọ́n rí ọmọ náà, àwọn tó ń dáko náà sọ fún ara wọn pé, ‘Ẹni tó máa jogún rẹ̀ nìyí.+ Ẹ wá, ẹ jẹ́ ká pa á, ká sì gba ogún rẹ̀!’ 39 Torí náà, wọ́n mú un, wọ́n jù ú sí ìta ọgbà àjàrà náà, wọ́n sì pa á.+ 40 Tí ẹni tó ni ọgbà àjàrà náà bá wá dé, kí ló máa ṣe fún àwọn tó ń dáko yẹn?” 41 Wọ́n sọ fún un pé: “Torí pé èèyàn burúkú ni wọ́n, ó máa mú ìparun tó lágbára* wá sórí wọn, ó sì máa gbé ọgbà àjàrà náà fún àwọn míì tó ń dáko, tí wọ́n máa fún un ní èso nígbà tí àkókò bá tó.”
42 Jésù sọ fún wọn pé: “Ṣé ẹ ò tíì kà á nínú Ìwé Mímọ́ rí pé, ‘Òkúta tí àwọn kọ́lékọ́lé kọ̀ sílẹ̀, òun ló wá di olórí òkúta igun ilé.*+ Ọ̀dọ̀ Jèhófà* ni èyí ti wá, ó sì jẹ́ ìyanu lójú wa’?+ 43 Ìdí nìyí tí mo fi sọ fún yín pé, a máa gba Ìjọba Ọlọ́run kúrò lọ́wọ́ yín, a sì máa fún orílẹ̀-èdè tó ń mú èso rẹ̀ jáde. 44 Bákan náà, ẹni tó bá kọ lu òkúta yìí máa fọ́ túútúú.+ Tó bá sì bọ́ lu ẹnikẹ́ni, ó máa rún ẹni náà wómúwómú.”+
45 Nígbà tí àwọn olórí àlùfáà àti àwọn Farisí gbọ́ àwọn àpèjúwe rẹ̀, wọ́n mọ̀ pé àwọn ló ń bá wí.+ 46 Bó tiẹ̀ jẹ́ pé wọ́n fẹ́ mú un,* wọ́n ń bẹ̀rù àwọn èrò, torí wòlíì ni àwọn èèyàn náà kà á sí.+
22 Jésù tún fi àwọn àpèjúwe bá wọn sọ̀rọ̀, ó sọ pé: 2 “A lè fi Ìjọba ọ̀run wé ọba kan tó se àsè ìgbéyàwó+ fún ọmọkùnrin rẹ̀. 3 Ó wá rán àwọn ẹrú rẹ̀ kí wọ́n lọ pe àwọn tí wọ́n pè síbi àsè ìgbéyàwó náà wá, àmọ́ wọn ò fẹ́ wá.+ 4 Ó tún rán àwọn ẹrú míì, ó sọ pé, ‘Ẹ sọ fún àwọn tí a pè, pé: “Ẹ wò ó! Mo ti pèsè oúnjẹ alẹ́ mi sílẹ̀, mo ti pa àwọn akọ màlúù mi àtàwọn ẹran mi tó sanra, gbogbo nǹkan sì ti wà ní sẹpẹ́. Ẹ wá síbi àsè ìgbéyàwó náà.”’ 5 Àmọ́ wọn ò kà á sí, wọ́n jáde lọ, ọ̀kan lọ sí oko rẹ̀, òmíràn lọ síbi òwò rẹ̀;+ 6 àmọ́ àwọn tó kù gbá àwọn ẹrú rẹ̀ mú, wọ́n kàn wọ́n lábùkù, wọ́n sì pa wọ́n.
7 “Inú bí ọba náà, ló bá rán àwọn ọmọ ogun rẹ̀ lọ pa àwọn apààyàn náà, ó sì dáná sun ìlú wọn.+ 8 Ó wá sọ fún àwọn ẹrú rẹ̀ pé, ‘Àsè ìgbéyàwó náà ti wà ní sẹpẹ́, àmọ́ àwọn tí a pè kò yẹ.+ 9 Torí náà, ẹ lọ sí àwọn ojú ọ̀nà tó jáde látinú ìlú, kí ẹ sì pe ẹnikẹ́ni tí ẹ bá rí wá síbi àsè ìgbéyàwó náà.’+ 10 Àwọn ẹrú náà ṣe bẹ́ẹ̀, wọ́n jáde lọ sí àwọn ojú ọ̀nà, wọ́n sì kó gbogbo àwọn tí wọ́n rí jọ, ẹni burúkú àti ẹni rere; àwọn tó ń jẹun* sì kún inú yàrá tí wọ́n ti ń ṣe ayẹyẹ ìgbéyàwó náà.
11 “Nígbà tí ọba náà wọlé wá wo àwọn àlejò, ó tajú kán rí ọkùnrin kan tí kò wọ aṣọ ìgbéyàwó. 12 Ó wá bi í pé, ‘Ọ̀gbẹ́ni, báwo lo ṣe wọlé síbí láìwọ aṣọ ìgbéyàwó?’ Ọkùnrin náà ò lè sọ nǹkan kan. 13 Ọba wá sọ fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pé, ‘Ẹ dè é tọwọ́ tẹsẹ̀, kí ẹ sì jù ú sínú òkùnkùn níta. Ibẹ̀ lá ti máa sunkún, tí á sì ti máa payín keke.’
14 “Torí ọ̀pọ̀ la pè, àmọ́ díẹ̀ la yàn.”
15 Àwọn Farisí wá lọ gbìmọ̀ pọ̀, kí wọ́n lè fi ọ̀rọ̀ rẹ̀ mú un.+ 16 Torí náà, wọ́n rán àwọn ọmọ ẹ̀yìn wọn sí i, pẹ̀lú àwọn ọmọ ẹgbẹ́ Hẹ́rọ́dù,+ wọ́n sọ pé: “Olùkọ́, a mọ̀ pé olóòótọ́ ni ọ́, ò ń kọ́ni ní ọ̀nà Ọlọ́run ní òtítọ́, o kì í wá ojúure ẹnikẹ́ni, torí kì í ṣe ìrísí àwọn èèyàn lò ń wò. 17 Torí náà, sọ fún wa, kí lèrò rẹ? Ṣé ó bófin mu* láti san owó orí fún Késárì àbí kò bófin mu?” 18 Àmọ́ Jésù mọ èrò burúkú wọn, ó sọ pé: “Ẹ̀yin alágàbàgebè, kí ló dé tí ẹ̀ ń dán mi wò? 19 Ẹ fi ẹyọ owó tí ẹ fi ń san owó orí hàn mí.” Wọ́n mú owó dínárì* kan wá fún un. 20 Ó sì sọ fún wọn pé: “Àwòrán àti àkọlé ta nìyí?” 21 Wọ́n sọ pé: “Ti Késárì ni.” Ó wá sọ fún wọn pé: “Torí náà, ẹ san àwọn ohun ti Késárì pa dà fún Késárì, àmọ́ ẹ fi àwọn ohun ti Ọlọ́run fún Ọlọ́run.”+ 22 Nígbà tí wọ́n gbọ́ ìyẹn, ó yà wọ́n lẹ́nu, wọ́n kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀, wọ́n sì lọ.
23 Lọ́jọ́ yẹn, àwọn Sadusí, tí wọ́n sọ pé kò sí àjíǹde,+ wá bi í pé:+ 24 “Olùkọ́, Mósè sọ pé: ‘Tí ọkùnrin èyíkéyìí bá kú láìní ọmọ, kí arákùnrin rẹ̀ fẹ́ ìyàwó rẹ̀, kó sì bímọ fún arákùnrin rẹ̀.’+ 25 Ó ṣẹlẹ̀ pé arákùnrin méje wà pẹ̀lú wa. Ẹni àkọ́kọ́ fẹ́ ìyàwó, ó sì kú, ó fi ìyàwó rẹ̀ sílẹ̀ fún arákùnrin rẹ̀, nígbà tó jẹ́ pé kò bí ọmọ kankan. 26 Ohun kan náà ló ṣẹlẹ̀ sí ẹnì kejì àti ẹnì kẹta, títí dórí ẹnì keje. 27 Nígbẹ̀yìn-gbẹ́yín, obìnrin náà kú. 28 Tí àwọn méjèèje bá wá jíǹde, èwo nínú wọn ló máa fẹ́? Torí gbogbo wọn ni wọ́n ti fi ṣe aya.”
29 Jésù dá wọn lóhùn pé: “Ẹ ti ṣàṣìṣe, torí pé ẹ ò mọ Ìwé Mímọ́, ẹ ò sì mọ agbára Ọlọ́run;+ 30 torí nígbà àjíǹde, àwọn ọkùnrin kì í gbéyàwó, a kì í sì í fa àwọn obìnrin fún ọkọ, àmọ́ wọ́n máa dà bí àwọn áńgẹ́lì ní ọ̀run.+ 31 Ní ti àjíǹde àwọn òkú, ṣé ẹ ò tíì ka ohun tí Ọlọ́run sọ fún yín ni, pé: 32 ‘Èmi ni Ọlọ́run Ábúráhámù, Ọlọ́run Ísákì àti Ọlọ́run Jékọ́bù’?+ Kì í ṣe Ọlọ́run àwọn òkú, àmọ́ ó jẹ́ Ọlọ́run àwọn alààyè.”+ 33 Nígbà tí àwọn èrò náà gbọ́ ìyẹn, bó ṣe ń kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ yà wọ́n lẹ́nu.+
34 Lẹ́yìn tí àwọn Farisí gbọ́ pé ó ti pa àwọn Sadusí lẹ́nu mọ́, wọ́n kóra jọ, wọ́n sì wá. 35 Ọ̀kan lára wọn, tó mọ Òfin dunjú, bi í ní ìbéèrè láti dán an wò: 36 “Olùkọ́, àṣẹ wo ló tóbi jù lọ nínú Òfin?”+ 37 Ó sọ fún un pé: “‘Kí o fi gbogbo ọkàn rẹ àti gbogbo ara* rẹ àti gbogbo èrò rẹ nífẹ̀ẹ́ Jèhófà* Ọlọ́run rẹ.’+ 38 Èyí ni àṣẹ tó tóbi jù lọ, tó sì jẹ́ àkọ́kọ́. 39 Ìkejì tó dà bíi rẹ̀ nìyí: ‘Kí o nífẹ̀ẹ́ ọmọnìkejì rẹ bí ara rẹ.’+ 40 Àṣẹ méjì yìí ni gbogbo Òfin àti àwọn Wòlíì rọ̀ mọ́.”+
41 Nígbà tí àwọn Farisí kóra jọ, Jésù bi wọ́n pé:+ 42 “Kí lèrò yín nípa Kristi? Ọmọ ta ni?” Wọ́n sọ fún un pé: “Ọmọ Dáfídì ni.”+ 43 Ó bi wọ́n pé: “Kí wá nìdí tí Dáfídì fi pè é ní Olúwa nípasẹ̀ ìmísí,+ tó sọ pé, 44 ‘Jèhófà* sọ fún Olúwa mi pé: “Jókòó sí ọwọ́ ọ̀tún mi, títí màá fi fi àwọn ọ̀tá rẹ sábẹ́ ẹsẹ̀ rẹ”’?+ 45 Tí Dáfídì bá pè é ní Olúwa, báwo ló ṣe jẹ́ ọmọ rẹ̀?”+ 46 Kò sẹ́ni tó lè dá a lóhùn rárá, láti ọjọ́ yẹn lọ, kò sẹ́ni tó jẹ́ bi í ní ìbéèrè mọ́.
23 Jésù wá bá àwọn èrò náà àti àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ sọ̀rọ̀, ó ní: 2 “Àwọn akọ̀wé òfin àti àwọn Farisí ti fi ara wọn sí orí ìjókòó Mósè. 3 Torí náà, gbogbo ohun tí wọ́n bá sọ fún yín ni kí ẹ ṣe, kí ẹ sì máa pa mọ́, àmọ́ ẹ má ṣe ohun tí wọ́n ń ṣe, torí tí wọ́n bá sọ̀rọ̀, wọn kì í ṣe ohun tí wọ́n sọ.+ 4 Wọ́n ń di àwọn ẹrù tó wúwo, wọ́n sì ń gbé e sí èjìká àwọn èèyàn,+ àmọ́ àwọn fúnra wọn ò ṣe tán láti fi ìka wọn sún un.+ 5 Torí kí àwọn èèyàn lè rí wọn ni wọ́n ṣe ń ṣe gbogbo ohun tí wọ́n ń ṣe,+ wọ́n fẹ àwọn akóló tí wọ́n ń kó ìwé mímọ́ sí, èyí tí wọ́n ń dè mọ́ra láti dáàbò bo ara wọn,*+ wọ́n sì mú kí wajawaja etí aṣọ wọn gùn.+ 6 Wọ́n fẹ́ràn ibi tó lọ́lá jù níbi oúnjẹ alẹ́ àti ìjókòó iwájú* nínú àwọn sínágọ́gù,+ 7 wọ́n fẹ́ràn kí wọ́n máa kí wọn níbi ọjà, kí àwọn èèyàn sì máa pè wọ́n ní Rábì.* 8 Àmọ́ ní tiyín, kí wọ́n má pè yín ní Rábì, torí Olùkọ́+ kan lẹ ní, arákùnrin sì ni gbogbo yín. 9 Bákan náà, ẹ má pe ẹnikẹ́ni ní baba yín ní ayé, torí Baba+ kan lẹ ní, Ẹni tó wà ní ọ̀run. 10 Kí wọ́n má sì pè yín ní aṣáájú, torí Aṣáájú kan lẹ ní, Kristi. 11 Àmọ́ kí ẹni tó tóbi jù lọ láàárín yín jẹ́ ìránṣẹ́ yín.+ 12 Ẹnikẹ́ni tó bá gbé ara rẹ̀ ga, a máa rẹ̀ ẹ́ sílẹ̀,+ ẹnikẹ́ni tó bá sì rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀, a máa gbé e ga.+
13 “Ẹ gbé, ẹ̀yin akọ̀wé òfin àti Farisí, ẹ̀yin alágàbàgebè! torí pé ẹ ti Ìjọba ọ̀run pa mọ́ àwọn èèyàn; ẹ̀yin fúnra yín ò wọlé, ẹ ò sì jẹ́ kí àwọn tó fẹ́ wọlé ráyè wọlé.+ 14* ——
15 “Ẹ gbé, ẹ̀yin akọ̀wé òfin àti Farisí, ẹ̀yin alágàbàgebè!+ torí pé ẹ̀ ń rìnrìn àjò gba orí òkun àti ilẹ̀ láti sọ ẹnì kan di aláwọ̀ṣe,* tó bá sì ti dà bẹ́ẹ̀, ẹ máa sọ ọ́ di ẹni tí Gẹ̀hẹ́nà* tọ́ sí ní ìlọ́po méjì jù yín lọ.
16 “Ẹ gbé, ẹ̀yin afọ́jú tó ń fini mọ̀nà,+ tó ń sọ pé, ‘Tí ẹnikẹ́ni bá fi tẹ́ńpìlì búra, kò ṣe nǹkan kan; àmọ́ tí ẹnikẹ́ni bá fi wúrà tẹ́ńpìlì búra, dandan ni kó ṣe ohun tó búra.’+ 17 Ẹ̀yin òmùgọ̀ àti afọ́jú! Ní tòótọ́, èwo ló tóbi jù, ṣé wúrà ni àbí tẹ́ńpìlì tó sọ wúrà di mímọ́? 18 Bákan náà, ‘Tí ẹnikẹ́ni bá fi pẹpẹ búra, kò ṣe nǹkan kan; àmọ́ tí ẹnikẹ́ni bá fi ẹ̀bùn tó wà lórí rẹ̀ búra, dandan ni kó ṣe ohun tó búra.’ 19 Ẹ̀yin afọ́jú! Èwo ló tóbi jù ní tòótọ́, ṣé ẹ̀bùn ni àbí pẹpẹ tó sọ ẹ̀bùn di mímọ́? 20 Torí náà, ẹnikẹ́ni tó bá fi pẹpẹ búra ń fi pẹpẹ náà àti gbogbo ohun tó wà lórí rẹ̀ búra; 21 ẹnikẹ́ni tó bá sì fi tẹ́ńpìlì búra ń fi tẹ́ńpìlì náà àti Ẹni tó ń gbé inú rẹ̀ búra;+ 22 ẹnikẹ́ni tó bá sì fi ọ̀run búra ń fi ìtẹ́ Ọlọ́run àti Ẹni tó jókòó sórí rẹ̀ búra.
23 “Ẹ gbé, ẹ̀yin akọ̀wé òfin àti Farisí, ẹ̀yin alágàbàgebè! torí pé ẹ̀ ń san ìdá mẹ́wàá ewéko míńtì, dílì àti kúmínì,+ àmọ́ ẹ ò ka àwọn ọ̀rọ̀ tó ṣe pàtàkì jù nínú Òfin sí, ìyẹn ìdájọ́ òdodo,+ àánú+ àti òtítọ́. Ó yẹ kí ẹ ṣe àwọn nǹkan yìí, àmọ́ kò yẹ kí ẹ ṣàìka àwọn nǹkan yòókù sí.+ 24 Ẹ̀yin afọ́jú tó ń fini mọ̀nà,+ tó ń sẹ́ kòkòrò tín-tìn-tín,*+ àmọ́ tó ń gbé ràkúnmí mì káló!+
25 “Ẹ gbé, ẹ̀yin akọ̀wé òfin àti Farisí, ẹ̀yin alágàbàgebè! torí pé ẹ̀ ń fọ ẹ̀yìn ife àti abọ́ mọ́,+ àmọ́ wọ̀bìà*+ àti ìkẹ́rabàjẹ́ kún inú wọn.+ 26 Farisí afọ́jú, kọ́kọ́ fọ inú ife àti abọ́ mọ́, kí ẹ̀yìn rẹ̀ náà lè mọ́.
27 “Ẹ gbé, ẹ̀yin akọ̀wé òfin àti Farisí, ẹ̀yin alágàbàgebè! + torí pé ẹ dà bí àwọn sàréè tí wọ́n kùn lẹ́fun,+ tí wọ́n rẹwà níta lóòótọ́, àmọ́ tó jẹ́ pé àwọn egungun òkú èèyàn àti onírúurú ohun àìmọ́ ló kún inú wọn. 28 Bẹ́ẹ̀ náà lẹ ṣe jẹ́ olódodo lójú àwọn èèyàn, àmọ́ ìwà àgàbàgebè kún inú yín, ẹ sì jẹ́ arúfin.+
29 “Ẹ gbé, ẹ̀yin akọ̀wé òfin àti Farisí, ẹ̀yin alágàbàgebè!+ torí pé ẹ̀ ń kọ́ sàréè àwọn wòlíì, ẹ sì ń ṣe ibojì* àwọn olódodo lọ́ṣọ̀ọ́,+ 30 ẹ sì sọ pé, ‘Ká ní a wà láyé nígbà ayé àwọn baba ńlá wa ni, a ò ní lọ́wọ́ sí bí wọ́n ṣe ta ẹ̀jẹ̀ àwọn wòlíì sílẹ̀.’ 31 Torí náà, ẹ̀ ń jẹ́rìí ta ko ara yín pé ọmọ àwọn tó pa àwọn wòlíì ni yín.+ 32 Tó bá rí bẹ́ẹ̀, ẹ mú kí òṣùwọ̀n àwọn baba ńlá yín kún.
33 “Ẹ̀yin ejò, ọmọ paramọ́lẹ̀,+ báwo lẹ ṣe máa bọ́ nínú ìdájọ́ Gẹ̀hẹ́nà?*+ 34 Torí èyí, mò ń rán àwọn wòlíì,+ àwọn amòye àtàwọn tó ń kọ́ni ní gbangba+ sí yín. Ẹ máa pa àwọn kan lára wọn,+ ẹ sì máa kàn wọ́n mọ́gi,* ẹ máa na àwọn kan lára wọn+ nínú àwọn sínágọ́gù yín, ẹ sì máa ṣe inúnibíni sí wọn+ láti ìlú dé ìlú, 35 kí ẹ lè jẹ̀bi ẹ̀jẹ̀ gbogbo àwọn olódodo tí wọ́n ta sílẹ̀ ní ayé, látorí ẹ̀jẹ̀ Ébẹ́lì+ olódodo dórí ẹ̀jẹ̀ Sekaráyà ọmọ Barakáyà, ẹni tí ẹ pa láàárín ibi mímọ́ àti pẹpẹ.+ 36 Lóòótọ́ ni mo sọ fún yín, gbogbo nǹkan yìí máa wá sórí ìran yìí.
37 “Jerúsálẹ́mù, Jerúsálẹ́mù, ìlú tó ń pa àwọn wòlíì, tó sì ń sọ àwọn tí a rán sí i lókùúta,+ wo bí mo ṣe máa ń fẹ́ kó àwọn ọmọ rẹ jọ tó lọ́pọ̀ ìgbà, bí ìgbà tí adìyẹ ń kó àwọn ọmọ rẹ̀ jọ sábẹ́ ìyẹ́ rẹ̀! Àmọ́ ẹ ò fẹ́ bẹ́ẹ̀.+ 38 Ẹ wò ó! A ti pa ilé yín tì fún yín.*+ 39 Torí mò ń sọ fún yín pé, ó dájú pé ẹ ò ní rí mi láti ìsinsìnyí títí ẹ fi máa sọ pé, ‘Ìbùkún ni fún ẹni tó ń bọ̀ ní orúkọ Jèhófà!’”*+
24 Bí Jésù ṣe ń kúrò ní tẹ́ńpìlì, àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ wá láti fi àwọn ilé tẹ́ńpìlì hàn án. 2 Ó sọ fún wọn pé: “Ṣebí ẹ rí gbogbo nǹkan yìí? Lóòótọ́ ni mo sọ fún yín, ó dájú pé wọn ò ní fi òkúta kan sílẹ̀ lórí òkúta míì níbí, láìwó o palẹ̀.”+
3 Nígbà tó jókòó sórí Òkè Ólífì, àwọn ọmọ ẹ̀yìn wá bá a ní òun nìkan, wọ́n sọ pé: “Sọ fún wa, ìgbà wo ni àwọn nǹkan yìí máa ṣẹlẹ̀, kí ló sì máa jẹ́ àmì pé o ti wà níhìn-ín*+ àti ti ìparí ètò àwọn nǹkan?”*+
4 Jésù dá wọn lóhùn pé: “Ẹ ṣọ́ra kí ẹnì kankan má ṣì yín lọ́nà,+ 5 torí ọ̀pọ̀ èèyàn máa wá ní orúkọ mi, wọ́n á sọ pé, ‘Èmi ni Kristi,’ wọ́n sì máa ṣi ọ̀pọ̀ èèyàn lọ́nà.+ 6 Ẹ máa gbọ́ nípa àwọn ogun, ẹ sì máa gbọ́ ìròyìn nípa àwọn ogun. Kí ẹ rí i pé ẹ ò bẹ̀rù, torí àwọn nǹkan yìí gbọ́dọ̀ ṣẹlẹ̀, àmọ́ òpin ò tíì dé.+
7 “Torí orílẹ̀-èdè máa dìde sí orílẹ̀-èdè àti ìjọba sí ìjọba,+ àìtó oúnjẹ+ àti ìmìtìtì ilẹ̀ sì máa wà láti ibì kan dé ibòmíì.+ 8 Gbogbo nǹkan yìí jẹ́ ìbẹ̀rẹ̀ wàhálà tó ń fa ìrora.
9 “Nígbà náà, àwọn èèyàn máa fà yín lé ìpọ́njú lọ́wọ́,+ wọ́n á sì pa yín,+ gbogbo orílẹ̀-èdè sì máa kórìíra yín nítorí orúkọ mi.+ 10 Bákan náà, ọ̀pọ̀ èèyàn ló máa kọsẹ̀ nígbà yẹn, wọ́n máa dalẹ̀ ara wọn, wọ́n á sì kórìíra ara wọn. 11 Ọ̀pọ̀lọpọ̀ wòlíì èké máa dìde, wọ́n sì máa ṣi ọ̀pọ̀ èèyàn lọ́nà;+ 12 torí pé ìwà tí kò bófin mu máa pọ̀ sí i, ìfẹ́ ọ̀pọ̀ jù lọ máa tutù. 13 Àmọ́ ẹni tó bá fara dà á* dé òpin máa rí ìgbàlà.+ 14 A ó sì wàásù ìhìn rere Ìjọba yìí ní gbogbo ilẹ̀ ayé tí à ń gbé, kó lè jẹ́ ẹ̀rí fún gbogbo orílẹ̀-èdè,+ nígbà náà ni òpin yóò dé.
15 “Torí náà, tí ẹ bá tajú kán rí ohun ìríra tó ń fa ìsọdahoro, tó dúró ní ibi mímọ́, bí wòlíì Dáníẹ́lì ṣe sọ ọ́+ (kí òǹkàwé lo òye), 16 nígbà náà, kí àwọn tó wà ní Jùdíà bẹ̀rẹ̀ sí í sá lọ sí àwọn òkè.+ 17 Kí ẹni tó wà lórí ilé má sọ̀ kalẹ̀ wá kó ẹrù kúrò nínú ilé rẹ̀, 18 kí ẹni tó wà ní pápá má sì pa dà wá mú aṣọ àwọ̀lékè rẹ̀. 19 Ó mà ṣe o, fún àwọn aláboyún àti àwọn tó ń tọ́ ọmọ jòjòló ní àwọn ọjọ́ yẹn o! 20 Ẹ máa gbàdúrà kí ìgbà tí ẹ máa sá má lọ bọ́ sí ìgbà òtútù tàbí ọjọ́ Sábáàtì; 21 torí ìpọ́njú ńlá máa wà nígbà náà,+ irú èyí tí kò tíì ṣẹlẹ̀ rí láti ìbẹ̀rẹ̀ ayé títí di báyìí, àní, irú rẹ̀ kò ní ṣẹlẹ̀ mọ́.+ 22 Kódà, ẹran ara kankan ò ní là á já, àfi tí a bá dín àwọn ọjọ́ yẹn kù; àmọ́ nítorí àwọn àyànfẹ́, a máa dín àwọn ọjọ́ yẹn kù.+
23 “Nígbà yẹn, tí ẹnikẹ́ni bá sọ fún yín pé, ‘Wò ó! Kristi wà níbí’+ tàbí ‘Lọ́hùn-ún!’ ẹ má gbà á gbọ́.+ 24 Torí àwọn èké Kristi àti àwọn wòlíì èké+ máa dìde, wọ́n sì máa ṣe àwọn iṣẹ́ àmì àti àwọn iṣẹ́ ìyanu tó lágbára, láti ṣi àwọn àyànfẹ́ pàápàá lọ́nà,+ tó bá ṣeé ṣe. 25 Ẹ wò ó! Mò ń kìlọ̀ fún yín ṣáájú. 26 Torí náà, tí àwọn èèyàn bá sọ fún yín pé, ‘Ẹ wò ó! Ó wà nínú aginjù,’ ẹ má lọ; ‘Ẹ wò ó! Ó wà nínú àwọn yàrá inú,’ ẹ má gbà á gbọ́.+ 27 Torí bí mànàmáná ṣe ń kọ láti ìlà oòrùn, tó sì ń mọ́lẹ̀ dé ìwọ̀ oòrùn, bẹ́ẹ̀ ló máa rí tí Ọmọ èèyàn bá ti wà níhìn-ín.*+ 28 Ibikíbi tí òkú bá wà, ibẹ̀ ni àwọn ẹyẹ idì máa kóra jọ sí.+
29 “Ẹsẹ̀kẹsẹ̀ lẹ́yìn ìpọ́njú àwọn ọjọ́ yẹn, oòrùn máa ṣókùnkùn,+ òṣùpá ò sì ní mọ́lẹ̀, àwọn ìràwọ̀ máa já bọ́ láti ọ̀run, a sì máa mi àwọn agbára ọ̀run.+ 30 Nígbà náà, àmì Ọmọ èèyàn máa fara hàn ní ọ̀run, ìbànújẹ́ máa mú kí gbogbo àwọn ẹ̀yà tó wà ní ayé lu ara wọn,+ wọ́n sì máa rí Ọmọ èèyàn+ tó ń bọ̀ lórí àwọsánmà* ojú ọ̀run pẹ̀lú agbára àti ògo ńlá.+ 31 Ó máa rán àwọn áńgẹ́lì rẹ̀ jáde pẹ̀lú ìró kàkàkí tó rinlẹ̀, wọ́n sì máa kó àwọn àyànfẹ́ rẹ̀ jọ látinú atẹ́gùn mẹ́rẹ̀ẹ̀rin, láti ìkángun kan ọ̀run títí dé ìkángun kejì.+
32 “Ní báyìí, ẹ kọ́ àpèjúwe yìí lára igi ọ̀pọ̀tọ́: Gbàrà tí ẹ̀ka rẹ̀ bá ṣẹ̀ṣẹ̀ yọ ọ̀mùnú, tó sì rúwé, ẹ mọ̀ pé ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn ti sún mọ́lé.+ 33 Bákan náà, tí ẹ bá rí gbogbo nǹkan yìí, kí ẹ mọ̀ pé ó ti sún mọ́ ẹnu ọ̀nà.+ 34 Lóòótọ́ ni mo sọ fún yín pé, ó dájú pé ìran yìí ò ní kọjá lọ títí gbogbo nǹkan yìí fi máa ṣẹlẹ̀. 35 Ọ̀run àti ayé máa kọjá lọ, àmọ́ ó dájú pé àwọn ọ̀rọ̀ mi ò ní kọjá lọ.+
36 “Ní ti ọjọ́ àti wákàtí yẹn, kò sí ẹni tó mọ̀ ọ́n,+ àwọn áńgẹ́lì ọ̀run àti Ọmọ pàápàá kò mọ̀ ọ́n, àfi Baba nìkan.+ 37 Torí bí àwọn ọjọ́ Nóà ṣe rí gẹ́lẹ́+ ló máa rí tí Ọmọ èèyàn bá ti wà níhìn-ín.*+ 38 Torí bó ṣe rí ní àwọn ọjọ́ yẹn ṣáájú Ìkún Omi, wọ́n ń jẹ, wọ́n sì ń mu, àwọn ọkùnrin ń gbéyàwó, a sì ń fa àwọn obìnrin fún ọkọ, títí di ọjọ́ tí Nóà wọ ọkọ̀ áàkì,+ 39 wọn ò fiyè sí i títí Ìkún Omi fi dé, tó sì gbá gbogbo wọn lọ,+ bẹ́ẹ̀ ló máa rí tí Ọmọ èèyàn bá ti wà níhìn-ín. 40 Nígbà yẹn, ọkùnrin méjì máa wà nínú pápá; a máa mú ọ̀kan lọ, a sì máa pa ìkejì tì. 41 Obìnrin méjì á máa lọ nǹkan lórí ọlọ; a máa mú ọ̀kan lọ, a sì máa pa ìkejì tì.+ 42 Torí náà, ẹ máa ṣọ́nà, torí pé ẹ ò mọ ọjọ́ tí Olúwa yín ń bọ̀.+
43 “Ṣùgbọ́n ẹ mọ ohun kan: Ká ní baálé ilé mọ ìṣọ́ tí olè ń bọ̀* ni,+ ì bá má sùn, kò sì ní jẹ́ kí wọ́n ráyè wọ ilé òun.+ 44 Torí èyí, kí ẹ̀yin náà múra sílẹ̀,+ torí wákàtí tí ẹ kò ronú pé ó máa jẹ́ ni Ọmọ èèyàn ń bọ̀.
45 “Ní tòótọ́, ta ni ẹrú olóòótọ́ àti olóye* tí ọ̀gá rẹ̀ yàn pé kó máa bójú tó àwọn ará ilé rẹ̀, kó máa fún wọn ní oúnjẹ wọn ní àkókò tó yẹ?+ 46 Aláyọ̀ ni ẹrú yẹn tí ọ̀gá rẹ̀ bá dé, tó sì rí i tó ń ṣe bẹ́ẹ̀!+ 47 Lóòótọ́ ni mo sọ fún yín, ó máa yàn án pé kó máa bójú tó gbogbo ohun ìní rẹ̀.
48 “Àmọ́ tí ẹrú burúkú yẹn bá lọ sọ nínú ọkàn rẹ̀ pé, ‘Ọ̀gá mi ń pẹ́,’+ 49 tó wá bẹ̀rẹ̀ sí í lu àwọn tí wọ́n jọ jẹ́ ẹrú, tó ń jẹ, tó sì ń mu pẹ̀lú àwọn ọ̀mùtí paraku, 50 ọ̀gá ẹrú yẹn máa dé ní ọjọ́ tí kò retí àti wákàtí tí kò mọ̀,+ 51 ó máa fi ìyà tó le jù lọ jẹ ẹ́, ó sì máa fi í sí àárín àwọn alágàbàgebè. Ibẹ̀ ni á ti máa sunkún, tí á sì ti máa payín keke.+
25 “A lè fi Ìjọba ọ̀run wé wúńdíá mẹ́wàá tí wọ́n mú fìtílà wọn,+ tí wọ́n sì jáde lọ pàdé ọkọ ìyàwó.+ 2 Márùn-ún nínú wọ́n jẹ́ òmùgọ̀, márùn-ún sì jẹ́ olóye.*+ 3 Àwọn òmùgọ̀ mú fìtílà wọn, àmọ́ wọn ò gbé òróró dání, 4 ṣùgbọ́n àwọn olóye rọ òróró sínú ìgò* wọn, wọ́n sì gbé fìtílà wọn dání. 5 Nígbà tí ọkọ ìyàwó ò tètè dé, gbogbo wọn tòògbé, wọ́n sì sùn lọ. 6 Ni ariwo bá sọ láàárín òru pé: ‘Ọkọ ìyàwó ti dé! Ẹ jáde lọ pàdé rẹ̀.’ 7 Gbogbo àwọn wúńdíá náà bá dìde, wọ́n sì tún fìtílà wọn ṣe.+ 8 Àwọn òmùgọ̀ sọ fún àwọn olóye pé, ‘Ẹ fún wa ní díẹ̀ nínú òróró yín, torí pé àwọn fìtílà wa ti fẹ́ kú.’ 9 Àwọn olóye dá wọn lóhùn pé: ‘Ó ṣeé ṣe kó má tó àwa àti ẹ̀yin. Torí náà, ẹ lọ sọ́dọ̀ àwọn tó ń tà á, kí ẹ sì ra tiyín.’ 10 Bí wọ́n ṣe ń lọ rà á, ọkọ ìyàwó dé. Àwọn wúńdíá tí wọ́n ti ṣe tán bá a wọlé síbi àsè ìgbéyàwó náà,+ a sì ti ilẹ̀kùn. 11 Lẹ́yìn náà, àwọn wúńdíá yòókù dé, wọ́n ní, ‘Ọ̀gá, Ọ̀gá, ṣílẹ̀kùn fún wa!’+ 12 Ó dá wọn lóhùn pé, ‘Kí n sọ òótọ́ fún yín, mi ò mọ̀ yín rí.’
13 “Torí náà, ẹ máa ṣọ́nà,+ torí pé ẹ ò mọ ọjọ́ tàbí wákàtí náà.+
14 “Torí ṣe ló dà bí ọkùnrin kan tó fẹ́ rìnrìn àjò lọ sí ilẹ̀ òkèèrè, tó wá pe àwọn ẹrú rẹ̀, tó sì fa àwọn ohun ìní rẹ̀ lé wọn lọ́wọ́.+ 15 Ó fún ọ̀kan ní tálẹ́ńtì* márùn-ún, ó fún òmíràn ní méjì, òmíràn ní ọ̀kan, ó fún kálukú bí agbára rẹ̀ ṣe mọ, ó sì lọ sí ilẹ̀ òkèèrè. 16 Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, ẹni tó gba tálẹ́ńtì márùn-ún lọ, ó fi ṣòwò, ó sì jèrè márùn-ún sí i. 17 Bákan náà, ẹni tó gba méjì jèrè méjì sí i. 18 Àmọ́ ẹrú tó gba ẹyọ kan ṣoṣo lọ, ó gbẹ́ ilẹ̀, ó sì fi owó* ọ̀gá rẹ̀ pa mọ́.
19 “Lẹ́yìn tó ti pẹ́ gan-an, ọ̀gá àwọn ẹrú yẹn dé, wọ́n sì jọ yanjú ọ̀rọ̀ owó.+ 20 Torí náà, ẹni tó gba tálẹ́ńtì márùn-ún wá, ó sì mú tálẹ́ńtì márùn-ún míì wá, ó ní, ‘Ọ̀gá, tálẹ́ńtì márùn-ún lo fún mi; wò ó, mo ti jèrè tálẹ́ńtì márùn-ún sí i.’+ 21 Ọ̀gá rẹ̀ sọ fún un pé: ‘O káre láé, ẹrú rere àti olóòótọ́! O jẹ́ olóòótọ́ lórí ohun díẹ̀. Màá fi ohun tó pọ̀ síkàáwọ́ rẹ.+ Bọ́ sínú ayọ̀ ọ̀gá rẹ.’+ 22 Lẹ́yìn náà, ẹni tó gba tálẹ́ńtì méjì wá, ó sì sọ pé, ‘Ọ̀gá, tálẹ́ńtì méjì lo fún mi; wò ó, mo ti jèrè tálẹ́ńtì méjì sí i.’+ 23 Ọ̀gá rẹ̀ sọ fún un pé: ‘O káre láé, ẹrú rere àti olóòótọ́! O jẹ́ olóòótọ́ lórí ohun díẹ̀. Màá fi ohun tó pọ̀ síkàáwọ́ rẹ. Bọ́ sínú ayọ̀ ọ̀gá rẹ.’
24 “Níkẹyìn, ẹrú tó gba tálẹ́ńtì kan wá, ó sì sọ pé: ‘Ọ̀gá, ẹni tó ṣòroó tẹ́ lọ́rùn ni mo mọ̀ ọ́ sí, o máa ń kárúgbìn níbi tí o ò fúnrúgbìn sí, o sì máa ń kó ọkà jọ níbi tí o ò ti fẹ́ ọkà.+ 25 Torí náà, ẹ̀rù bà mí, mo sì lọ fi tálẹ́ńtì rẹ pa mọ́ sínú ilẹ̀. Wò ó, gba nǹkan rẹ.’ 26 Ọ̀gá rẹ̀ fún un lésì pé: ‘Ẹrú burúkú tó ń lọ́ra, o mọ̀ àbí, pé mò ń kárúgbìn níbi tí mi ò fúnrúgbìn sí, mo sì ń kó ọkà jọ níbi tí mi ò ti fẹ́ ọkà? 27 Tó bá rí bẹ́ẹ̀, ó yẹ kí o ti kó owó* mi lọ sí báǹkì, tí mo bá sì dé, ǹ bá ti gbà á pẹ̀lú èlé.
28 “‘Torí náà, ẹ gba tálẹ́ńtì náà lọ́wọ́ rẹ̀, kí ẹ sì fún ẹni tó ní tálẹ́ńtì mẹ́wàá.+ 29 Torí gbogbo ẹni tó bá ní, a máa fi kún èyí tó ní, ó sì máa ní ọ̀pọ̀ yanturu. Àmọ́ ẹni tí kò bá ní, a máa gba èyí tó ní pàápàá kúrò lọ́wọ́ rẹ̀.+ 30 Ẹ ju ẹrú tí kò dáa fún ohunkóhun náà sínú òkùnkùn níta. Ibẹ̀ lá ti máa sunkún, tí á sì ti máa payín keke.’
31 “Tí Ọmọ èèyàn+ bá dé nínú ògo rẹ̀, tòun ti gbogbo áńgẹ́lì pẹ̀lú rẹ̀, nígbà náà,+ ó máa jókòó sórí ìtẹ́ ògo rẹ̀. 32 A máa kó gbogbo orílẹ̀-èdè jọ síwájú rẹ̀, ó sì máa ya àwọn èèyàn sọ́tọ̀ọ̀tọ̀, bí olùṣọ́ àgùntàn ṣe ń ya àgùntàn sọ́tọ̀ kúrò lára ewúrẹ́. 33 Ó máa kó àwọn àgùntàn+ sí ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀, àmọ́ ó máa kó àwọn ewúrẹ́ sí òsì rẹ̀.+
34 “Ọba máa wá sọ fún àwọn tó wà ní ọ̀tún rẹ̀ pé: ‘Ẹ wá, ẹ̀yin tí Baba mi ti bù kún, ẹ jogún Ìjọba tí a ti pèsè sílẹ̀ fún yín látìgbà ìpìlẹ̀ ayé. 35 Torí ebi pa mí, ẹ sì fún mi ní oúnjẹ; òùngbẹ gbẹ mí, ẹ sì fún mi ní nǹkan mu. Mo jẹ́ àjèjì, ẹ sì gbà mí lálejò;+ 36 mo wà ní ìhòòhò,* ẹ sì fi aṣọ wọ̀ mí.+ Mo ṣàìsàn, ẹ sì tọ́jú mi. Mo wà lẹ́wọ̀n, ẹ sì wá wò mí.’+ 37 Àwọn olódodo máa wá dá a lóhùn pé: ‘Olúwa, ìgbà wo la rí ọ tí ebi ń pa ọ́, tí a sì fún ọ ní oúnjẹ tàbí tí òùngbẹ ń gbẹ ọ́, tí a sì fún ọ ní nǹkan mu?+ 38 Ìgbà wo la rí ọ ní àjèjì, tí a sì gbà ọ́ lálejò tàbí tí o wà ní ìhòòhò, tí a sì fi aṣọ wọ̀ ọ́? 39 Ìgbà wo la rí ọ tí ò ń ṣàìsàn tàbí tí o wà lẹ́wọ̀n, tí a sì wá wò ọ́?’ 40 Ọba máa dá wọn lóhùn pé, ‘Lóòótọ́ ni mo sọ fún yín, torí pé ẹ ti ṣe é fún ọ̀kan lára àwọn arákùnrin mi tó kéré jù lọ yìí, ẹ ti ṣe é fún mi.’+
41 “Ó máa wá sọ fún àwọn tó wà ní òsì rẹ̀ pé: ‘Ẹ kúrò lọ́dọ̀ mi,+ ẹ̀yin tí a ti gégùn-ún fún, ẹ lọ sínú iná àìnípẹ̀kun+ tí a ṣètò sílẹ̀ fún Èṣù àti àwọn áńgẹ́lì rẹ̀.+ 42 Nítorí ebi pa mí, àmọ́ ẹ ò fún mi ní oúnjẹ; òùngbẹ gbẹ mí, àmọ́ ẹ ò fún mi ní nǹkan kan mu. 43 Mo jẹ́ àjèjì, àmọ́ ẹ ò gbà mí lálejò; mo wà ní ìhòòhò, àmọ́ ẹ ò fi aṣọ wọ̀ mí; mo ṣàìsàn, mo sì wà lẹ́wọ̀n, àmọ́ ẹ ò tọ́jú mi.’ 44 Àwọn náà á fi ọ̀rọ̀ yìí dá a lóhùn pé: ‘Olúwa, ìgbà wo la rí ọ tí ebi ń pa ọ́ tàbí tí òùngbẹ ń gbẹ ọ́ tàbí tí o jẹ́ àjèjì tàbí tí o wà ní ìhòòhò tàbí tí ò ń ṣàìsàn tàbí tí o wà lẹ́wọ̀n, tí a kò sì ṣe ìránṣẹ́ fún ọ?’ 45 Ó máa dá wọn lóhùn pé: ‘Lóòótọ́ ni mo sọ fún yín, torí pé ẹ ò ṣe é fún ọ̀kan nínú àwọn tó kéré jù lọ yìí, ẹ ò ṣe é fún mi.’+ 46 Àwọn yìí máa lọ sínú ìparun* àìnípẹ̀kun,+ ṣùgbọ́n àwọn olódodo sínú ìyè àìnípẹ̀kun.”+
26 Nígbà tí Jésù sọ gbogbo ọ̀rọ̀ yìí tán, ó sọ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: 2 “Ẹ mọ̀ pé ní ọjọ́ méjì òní, Ìrékọjá máa wáyé,+ a sì máa fa Ọmọ èèyàn léni lọ́wọ́, kí wọ́n lè kàn án mọ́gi.”+
3 Àwọn olórí àlùfáà àti àwọn àgbààgbà àwọn èèyàn náà wá kóra jọ sínú àgbàlá àlùfáà àgbà, tí wọ́n ń pè ní Káyáfà,+ 4 wọ́n sì gbìmọ̀ pọ̀+ kí wọ́n lè fi ọgbọ́n àrékérekè* mú* Jésù, kí wọ́n sì pa á. 5 Àmọ́ wọ́n sọ pé: “Kì í ṣe nígbà àjọyọ̀, kí ariwo má bàa sọ láàárín àwọn èèyàn.”
6 Nígbà tí Jésù wà ní Bẹ́tánì, ní ilé Símónì adẹ́tẹ̀,+ 7 obìnrin kan tó ní orùba* alabásítà tí wọ́n rọ òróró onílọ́fínńdà olówó iyebíye sí wá sọ́dọ̀ rẹ̀, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í da òróró náà sí orí rẹ̀ nígbà tó ń jẹun.* 8 Nígbà tí àwọn ọmọ ẹ̀yìn rí èyí, inú bí wọn gan-an, wọ́n sì sọ pé: “Kí ló dé tó ń fi nǹkan ṣòfò báyìí? 9 Ṣe là bá tà á ní owó gọbọi, ká sì fún àwọn aláìní.” 10 Jésù mọ ohun tí wọ́n ń sọ, ó wá sọ fún wọn pé: “Kí ló dé tí ẹ fẹ́ máa yọ obìnrin yìí lẹ́nu? Ohun tó dáa gan-an ló ṣe sí mi. 11 Torí ìgbà gbogbo ni àwọn aláìní wà láàárín yín,+ àmọ́ ìgbà gbogbo kọ́ ni màá wà láàárín yín.+ 12 Nígbà tí obìnrin yìí da òróró onílọ́fínńdà yìí sí ara mi, ó ṣe é kó lè múra mi sílẹ̀ fún ìsìnkú.+ 13 Lóòótọ́ ni mo sọ fún yín, ibikíbi tí a bá ti ń wàásù ìhìn rere yìí ní gbogbo ayé, wọ́n á máa sọ ohun tí obìnrin yìí ṣe láti fi rántí rẹ̀.”+
14 Lẹ́yìn náà, ọ̀kan nínú àwọn Méjìlá náà, tí wọ́n ń pè ní Júdásì Ìsìkáríọ́tù,+ lọ sọ́dọ̀ àwọn olórí àlùfáà,+ 15 ó sì sọ pé: “Kí lẹ máa fún mi, kí n lè fà á lé yín lọ́wọ́?”+ Wọ́n bá a ṣe àdéhùn ọgbọ̀n (30) ẹyọ fàdákà.+ 16 Torí náà, látìgbà yẹn lọ, ó ń wá ìgbà tó máa dáa jù láti fà á lé wọn lọ́wọ́.
17 Ní ọjọ́ kìíní Àjọyọ̀ Búrẹ́dì Aláìwú,+ àwọn ọmọ ẹ̀yìn wá sọ́dọ̀ Jésù, wọ́n bi í pé: “Ibo lo fẹ́ ká ṣètò fún ọ láti jẹ Ìrékọjá?”+ 18 Ó dáhùn pé: “Ẹ lọ sínú ìlú, kí ẹ lọ bá Lágbájá, kí ẹ sì sọ fún un pé, ‘Olùkọ́ sọ pé: “Àkókò tí a yàn fún mi ti sún mọ́lé; èmi àti àwọn ọmọ ẹ̀yìn mi máa ṣe ayẹyẹ Ìrékọjá ní ilé rẹ.”’” 19 Torí náà, àwọn ọmọ ẹ̀yìn ṣe ohun tí Jésù sọ fún wọn gẹ́lẹ́, wọ́n sì múra sílẹ̀ fún Ìrékọjá.
20 Nígbà tó di ìrọ̀lẹ́,+ òun àti àwọn ọmọ ẹ̀yìn méjìlá (12) jókòó* sídìí tábìlì.+ 21 Nígbà tí wọ́n ń jẹun, ó sọ pé: “Lóòótọ́ ni mo sọ fún yín, ọ̀kan nínú yín máa dà mí.”+ 22 Ọ̀rọ̀ yìí bà wọ́n lọ́kàn jẹ́ gan-an, gbogbo wọn wá bẹ̀rẹ̀ sí í sọ fún un lọ́kọ̀ọ̀kan pé: “Olúwa, èmi kọ́ o, àbí èmi ni?” 23 Ó fún wọn lésì pé: “Ẹni tí a jọ ń ki ọwọ́ bọ inú abọ́ ni ẹni tó máa dà mí.+ 24 Lóòótọ́, Ọmọ èèyàn ń lọ, bí a ṣe kọ ọ́ nípa rẹ̀, àmọ́ ọkùnrin tí a tipasẹ̀ rẹ̀ fi Ọmọ èèyàn léni lọ́wọ́+ gbé!+ Ì bá sàn fún ọkùnrin náà ká ní wọn ò bí i.”+ 25 Júdásì, ẹni tó máa tó dà á, sọ pé: “Èmi kọ́ o, àbí èmi ni, Rábì?” Jésù sọ fún un pé: “Ìwọ fúnra rẹ ti sọ ọ́.”
26 Bí wọ́n ṣe ń jẹun, Jésù mú búrẹ́dì, lẹ́yìn tó súre, ó bù ú,+ ó sì fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn, ó sọ pé: “Ẹ gbà, kí ẹ jẹ ẹ́. Èyí túmọ̀ sí ara mi.”+ 27 Ó mú ife kan, ó dúpẹ́, ó sì gbé e fún wọn, ó ní: “Gbogbo yín, ẹ mu nínú rẹ̀,+ 28 torí èyí túmọ̀ sí ‘ẹ̀jẹ̀+ májẹ̀mú’ mi,+ tí a máa dà jáde nítorí ọ̀pọ̀ èèyàn,+ kí wọ́n lè rí ìdáríjì àwọn ẹ̀ṣẹ̀.+ 29 Àmọ́ mò ń sọ fún yín pé: Ó dájú pé mi ò tún ní mu èyíkéyìí nínú àwọn ohun tí wọ́n fi àjàrà ṣe yìí, títí di ọjọ́ yẹn tí màá mu ún ní tuntun pẹ̀lú yín nínú Ìjọba Baba mi.”+ 30 Níkẹyìn, lẹ́yìn tí wọ́n kọrin ìyìn,* wọ́n lọ sí Òkè Ólífì.+
31 Jésù sọ fún wọn pé: “Gbogbo yín lẹ máa kọsẹ̀ torí ohun tó máa ṣẹlẹ̀ sí mi lóru òní, torí a ti kọ ọ́ pé: ‘Màá kọ lu olùṣọ́ àgùntàn, àwọn àgùntàn inú agbo sì máa tú ká.’+ 32 Àmọ́ lẹ́yìn tí mo bá jíǹde, màá lọ sí Gálílì ṣáájú yín.”+ 33 Ṣùgbọ́n Pétérù dá a lóhùn pé: “Tí gbogbo àwọn yòókù bá tiẹ̀ kọsẹ̀ torí ohun tó máa ṣẹlẹ̀ sí ọ, ó dájú pé èmi ò ní kọsẹ̀ láé!”+ 34 Jésù sọ fún un pé: “Lóòótọ́ ni mo sọ fún ọ, lóru òní, kí àkùkọ tó kọ, o máa sẹ́ mi lẹ́ẹ̀mẹta.”+ 35 Pétérù sọ fún un pé: “Àní tó bá tiẹ̀ gba pé kí n kú pẹ̀lú rẹ pàápàá, ó dájú pé mi ò ní sẹ́ ọ.”+ Gbogbo àwọn ọmọ ẹ̀yìn yòókù sọ ohun kan náà.
36 Lẹ́yìn náà, Jésù àti àwọn ọmọ ẹ̀yìn jọ wá sí ibi tí wọ́n ń pè ní Gẹ́tísémánì,+ ó sì sọ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn pé: “Ẹ jókòó síbí, mo fẹ́ lọ sí ọ̀hún yẹn lọ gbàdúrà.”+ 37 Ó mú Pétérù àti àwọn ọmọ Sébédè méjèèjì dání, ó bẹ̀rẹ̀ sí í ní ẹ̀dùn ọkàn, ìdààmú sì bá a gan-an.+ 38 Ó wá sọ fún wọn pé: “Ẹ̀dùn ọkàn bá mi* gan-an, àní títí dé ikú. Ẹ dúró síbí, kí ẹ sì máa ṣọ́nà pẹ̀lú mi.”+ 39 Ó lọ síwájú díẹ̀, ó dojú bolẹ̀, ó sì gbàdúrà pé:+ “Baba mi, tó bá ṣeé ṣe, jẹ́ kí ife+ yìí ré mi kọjá. Síbẹ̀, kì í ṣe bí mo ṣe fẹ́, àmọ́ bí ìwọ ṣe fẹ́.”+
40 Ó pa dà sọ́dọ̀ àwọn ọmọ ẹ̀yìn, ó sì rí i pé wọ́n ń sùn, ó wá sọ fún Pétérù pé: “Ṣé ẹ ò wá lè ṣọ́nà pẹ̀lú mi fún wákàtí kan péré ni?+ 41 Ẹ máa ṣọ́nà,+ kí ẹ sì máa gbàdúrà nígbà gbogbo,+ kí ẹ má bàa kó sínú ìdẹwò.+ Ní tòótọ́, ẹ̀mí ń fẹ́,* àmọ́ ẹran ara jẹ́ aláìlera.”+ 42 Ó tún lọ gbàdúrà lẹ́ẹ̀kejì, ó sọ pé: “Baba mi, tí kò bá ṣeé ṣe kí èyí kọjá lọ àfi tí mo bá mu ún, jẹ́ kí ìfẹ́ rẹ ṣẹ.”+ 43 Ó tún pa dà wá, ó sì rí i pé wọ́n ń sùn, torí oorun ń kùn wọ́n gan-an. 44 Ó wá fi wọ́n sílẹ̀, ó tún lọ gbàdúrà lẹ́ẹ̀kẹta, ó sì sọ ohun kan náà lẹ́ẹ̀kan sí i. 45 Nígbà tó pa dà sọ́dọ̀ àwọn ọmọ ẹ̀yìn, ó sọ fún wọn pé: “Ní irú àkókò yìí, ẹ̀ ń sùn, ẹ sì ń sinmi! Ẹ wò ó! Wákàtí náà ti dé tán tí wọ́n máa fi Ọmọ èèyàn lé àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ lọ́wọ́. 46 Ẹ dìde, ẹ jẹ́ ká lọ. Ẹ wò ó! Ẹni tó máa dà mí ti dé tán.” 47 Bó ṣe ń sọ̀rọ̀ lọ́wọ́, wò ó! Júdásì, ọ̀kan lára àwọn Méjìlá náà dé pẹ̀lú èrò rẹpẹtẹ tí wọ́n kó idà àti kùmọ̀ dání, àwọn olórí àlùfáà àti àwọn àgbààgbà àwọn èèyàn náà ló rán wọn wá.+
48 Ẹni tó fẹ́ dà á ti fún wọn ní àmì kan, ó ní: “Ẹnikẹ́ni tí mo bá fẹnu kò lẹ́nu, òun ni ẹni náà; kí ẹ mú un.” 49 Ó wá lọ tààràtà sọ́dọ̀ Jésù, ó sọ pé: “Mo kí ọ o, Rábì!” ó sì rọra fi ẹnu kò ó lẹ́nu. 50 Àmọ́ Jésù sọ fún un pé: “Ọ̀gbẹ́ni, kí lo wá ṣe níbí?”+ Ni wọ́n bá wá síwájú, wọ́n gbá Jésù mú, wọ́n sì mú un sọ́dọ̀. 51 Àmọ́ wò ó! ọ̀kan lára àwọn tó wà pẹ̀lú Jésù na ọwọ́ rẹ̀, ó fa idà rẹ̀ yọ, ó sì ṣá ẹrú àlùfáà àgbà, ó gé etí rẹ̀ dà nù.+ 52 Jésù wá sọ fún un pé: “Dá idà rẹ pa dà sí àyè rẹ̀,+ torí gbogbo àwọn tó bá yọ idà máa ṣègbé nípasẹ̀ idà.+ 53 Àbí o rò pé mi ò lè bẹ Baba mi pé kó fún mi ní àwọn áńgẹ́lì tó ju líjíónì méjìlá (12) lọ ní ìṣẹ́jú yìí?+ 54 Tó bá rí bẹ́ẹ̀, báwo ni Ìwé Mímọ́ tó sọ pé ó gbọ́dọ̀ ṣẹlẹ̀ báyìí ṣe máa ṣẹ?” 55 Ní wákàtí yẹn, Jésù sọ fún àwọn èrò náà pé: “Ṣé èmi lẹ wá fi idà àti kùmọ̀ mú bí olè? Ojoojúmọ́ ni mò ń jókòó nínú tẹ́ńpìlì,+ tí mò ń kọ́ni, àmọ́ ẹ ò mú mi.+ 56 Ṣùgbọ́n gbogbo èyí ṣẹlẹ̀ kí ohun* tí àwọn wòlíì kọ sílẹ̀ lè ṣẹ.” Gbogbo àwọn ọmọ ẹ̀yìn wá fi í sílẹ̀,+ wọ́n sì sá lọ.+
57 Àwọn tó mú Jésù wá mú un lọ sọ́dọ̀ Káyáfà+ tó jẹ́ àlùfáà àgbà, níbi tí àwọn akọ̀wé òfin àti àwọn àgbààgbà kóra jọ sí.+ 58 Àmọ́ Pétérù ń tẹ̀ lé e ní òkèèrè, títí dé àgbàlá àlùfáà àgbà, lẹ́yìn tó sì wọlé, ó jókòó sọ́dọ̀ àwọn ìránṣẹ́ ilé náà kó lè mọ ibi tọ́rọ̀ yẹn máa já sí.+
59 Àwọn olórí àlùfáà àti gbogbo Sàhẹ́ndìrìn ń wá ẹ̀rí èké tí wọ́n máa fi mú Jésù kí wọ́n lè pa á.+ 60 Àmọ́ wọn ò rí ìkankan, bó tiẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ ẹlẹ́rìí èké ló jáde wá.+ Nígbà tó yá, àwọn méjì wá síwájú, 61 wọ́n sọ pé: “Ọkùnrin yìí sọ pé, ‘Mo lè wó tẹ́ńpìlì Ọlọ́run palẹ̀, kí n sì fi ọjọ́ mẹ́ta kọ́ ọ.’”+ 62 Ni àlùfáà àgbà bá dìde, ó sì sọ fún un pé: “Ṣé o ò ní fèsì rárá ni? Ẹ̀rí tí àwọn èèyàn yìí jẹ́ lòdì sí ọ yìí ńkọ́?”+ 63 Àmọ́ Jésù ò sọ̀rọ̀.+ Àlùfáà àgbà wá sọ fún un pé: “Mo fi ọ́ sábẹ́ ìbúra níwájú Ọlọ́run alààyè pé kí o sọ fún wa bóyá ìwọ ni Kristi, Ọmọ Ọlọ́run!”+ 64 Jésù sọ fún un pé: “Ìwọ fúnra rẹ ti sọ ọ́. Àmọ́ mò ń sọ fún yín pé: Láti ìsinsìnyí lọ, ẹ máa rí Ọmọ èèyàn+ tó jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún agbára,+ tó sì ń bọ̀ lórí àwọn àwọsánmà* ojú ọ̀run.”+ 65 Àlùfáà àgbà fa aṣọ àwọ̀lékè rẹ̀ ya, ó ní: “Ó ti sọ̀rọ̀ òdì! Kí la tún fẹ́ fi àwọn ẹlẹ́rìí ṣe? Ẹ wò ó! Ẹ ti gbọ́ ọ̀rọ̀ òdì náà. 66 Kí lèrò yín?” Wọ́n fèsì pé: “Ikú ló tọ́ sí i.”+ 67 Wọ́n wá tutọ́ sí i lójú,+ wọ́n sì gbá a ní ẹ̀ṣẹ́.+ Àwọn míì gbá a lójú,+ 68 wọ́n ní: “Sọ tẹ́lẹ̀ fún wa, ìwọ Kristi. Ta ló gbá ọ?”
69 Pétérù jókòó síta nínú àgbàlá, ìránṣẹ́bìnrin kan sì wá sọ́dọ̀ rẹ̀, ó ní: “Ìwọ náà wà pẹ̀lú Jésù ará Gálílì!”+ 70 Àmọ́ ó sẹ́ níwájú gbogbo wọn, ó ní: “Mi ò mọ ohun tí ò ń sọ.” 71 Nígbà tó jáde lọ sí ilé ẹnu ọ̀nà, ọmọbìnrin míì tún kíyè sí i, ó sì sọ fún àwọn tó wà níbẹ̀ pé: “Ọkùnrin yìí wà pẹ̀lú Jésù ará Násárẹ́tì.”+ 72 Ló bá tún sẹ́, ó sì búra pé: “Mi ò mọ ọkùnrin náà!” 73 Lẹ́yìn tó ṣe díẹ̀, àwọn tó dúró sí àyíká wá, wọ́n sì sọ fún Pétérù pé: “Ó dájú pé ìwọ náà wà lára wọn, torí ká sòótọ́, èdè ẹnu rẹ* tú ọ fó.” 74 Ó wá bẹ̀rẹ̀ sí í gégùn-ún, ó sì ń búra pé: “Mi ò mọ ọkùnrin náà!” Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, àkùkọ kọ. 75 Pétérù wá rántí ohun tí Jésù sọ, pé: “Kí àkùkọ tó kọ, o máa sẹ́ mi lẹ́ẹ̀mẹta.”+ Ló bá bọ́ síta, ó sì sunkún gidigidi.
27 Nígbà tó di àárọ̀, gbogbo àwọn olórí àlùfáà àti àwọn àgbààgbà àwọn èèyàn náà gbìmọ̀ pọ̀ kí wọ́n lè pa Jésù.+ 2 Lẹ́yìn tí wọ́n dè é, wọ́n mú un lọ, wọ́n sì fà á lé Pílátù lọ́wọ́, òun ni gómìnà.+
3 Nígbà tí Júdásì, ẹni tó dà á, rí i pé wọ́n ti dá Jésù lẹ́bi, ẹ̀dùn ọkàn bá a, ó sì kó ọgbọ̀n (30) ẹyọ fàdákà náà pa dà wá fún àwọn olórí àlùfáà àti àwọn àgbààgbà,+ 4 ó sọ pé: “Mo dẹ́ṣẹ̀ nígbà tí mo fi ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ lé yín lọ́wọ́.” Wọ́n sọ pé: “Kí ló kàn wá pẹ̀lú ìyẹn? Ìwọ ni kí o lọ wá nǹkan ṣe sí i!”* 5 Torí náà, ó da àwọn ẹyọ fàdákà náà sínú tẹ́ńpìlì, ó sì kúrò níbẹ̀. Ó wá lọ pokùn so.+ 6 Àmọ́ àwọn olórí àlùfáà kó àwọn ẹyọ fàdákà náà, wọ́n sì sọ pé: “Kò bófin mu ká kó o sí ibi ìṣúra mímọ́, torí pé owó ẹ̀jẹ̀ ni.” 7 Lẹ́yìn tí wọ́n gbìmọ̀ pọ̀, wọ́n fi owó náà ra pápá amọ̀kòkò, kí wọ́n lè máa sin àwọn àjèjì síbẹ̀. 8 Torí náà, Pápá Ẹ̀jẹ̀+ ni wọ́n ń pe pápá náà títí dòní yìí. 9 Ìgbà yẹn ni ohun tí a sọ nípasẹ̀ wòlíì Jeremáyà ṣẹ pé: “Wọ́n kó ọgbọ̀n (30) ẹyọ fàdákà, iye owó tí wọ́n dá lé ọkùnrin náà, ẹni tí àwọn kan lára àwọn ọmọ Ísírẹ́lì dá iye owó kan lé, 10 wọ́n sì fi ra pápá amọ̀kòkò, gẹ́gẹ́ bí ohun tí Jèhófà* pa láṣẹ fún mi.”+
11 Jésù wá dúró níwájú gómìnà, gómìnà sì bi í pé: “Ṣé ìwọ ni Ọba Àwọn Júù?” Jésù fèsì pé: “Ìwọ fúnra rẹ ti sọ ọ́.”+ 12 Àmọ́ bí àwọn olórí àlùfáà àti àwọn àgbààgbà ṣe ń fẹ̀sùn kàn án, kò dáhùn.+ 13 Pílátù wá bi í pé: “Ṣé o ò gbọ́ bí ẹ̀rí tí wọ́n ń jẹ́ lòdì sí ọ ṣe pọ̀ tó ni?” 14 Àmọ́ kò dá a lóhùn, àní kò sọ nǹkan kan, débi pé ó ya gómìnà náà lẹ́nu gan-an.
15 Tí wọ́n bá ń ṣe àjọyọ̀, ó jẹ́ àṣà gómìnà láti tú ẹlẹ́wọ̀n kan sílẹ̀ fún àwọn èèyàn, ẹnikẹ́ni tí wọ́n bá fẹ́.+ 16 Àkókò yẹn gan-an ni ẹlẹ́wọ̀n burúkú kan tó lókìkí wà ní àhámọ́ wọn, Bárábà lorúkọ rẹ̀. 17 Torí náà, nígbà tí wọ́n kóra jọ, Pílátù sọ fún wọn pé: “Ta lẹ fẹ́ kí n tú sílẹ̀ fún yín, ṣé Bárábà ni àbí Jésù tí wọ́n ń pè ní Kristi?” 18 Torí Pílátù mọ̀ pé wọ́n ń ṣe ìlara rẹ̀ ni wọ́n ṣe fà á lé òun lọ́wọ́. 19 Bákan náà, nígbà tó jókòó sórí ìjókòó ìdájọ́, ìyàwó rẹ̀ ránṣẹ́ sí i pé: “Má ṣe ní ohunkóhun ṣe pẹ̀lú ọkùnrin olódodo yẹn, torí mo jìyà gan-an lójú àlá lónìí nítorí rẹ̀.” 20 Àmọ́ àwọn olórí àlùfáà àti àwọn àgbààgbà rọ àwọn èrò náà pé kí wọ́n sọ pé Bárábà ni àwọn fẹ́,+ àmọ́ kí wọ́n pa Jésù.+ 21 Gómìnà dá wọn lóhùn pé: “Èwo nínú àwọn méjèèjì lẹ fẹ́ kí n tú sílẹ̀ fún yín?” Wọ́n sọ pé: “Bárábà.” 22 Pílátù sọ fún wọn pé: “Kí wá ni kí n ṣe sí Jésù tí wọ́n ń pè ní Kristi?” Gbogbo wọ́n sọ pé: “Kàn án mọ́gi!”*+ 23 Ó sọ pé: “Kí ló dé? Nǹkan burúkú wo ló ṣe?” Síbẹ̀, wọ́n túbọ̀ ń kígbe ṣáá pé: “Kàn án mọ́gi!”+
24 Nígbà tó rí i pé òun ò rí nǹkan kan ṣe sí i, àmọ́ tí ariwo ń sọ, Pílátù bu omi, ó sì wẹ ọwọ́ rẹ̀ níwájú àwọn èrò náà, ó sọ pé: “Ọwọ́ mi mọ́ kúrò nínú ẹ̀jẹ̀ ọkùnrin yìí. Ẹ̀yin fúnra yín ni kí ẹ lọ wá nǹkan ṣe sí i.” 25 Ni gbogbo àwọn èèyàn náà bá dá a lóhùn pé: “Kí ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ wá sórí àwa àti àwọn ọmọ wa.”+ 26 Ó wá tú Bárábà sílẹ̀ fún wọn, àmọ́ ó ní kí wọ́n na Jésù,+ ó sì fà á lé wọn lọ́wọ́ kí wọ́n lè kàn án mọ́gi.+
27 Àwọn ọmọ ogun gómìnà wá mú Jésù wọnú ilé gómìnà, wọ́n sì kó gbogbo ọ̀wọ́ àwọn ọmọ ogun jọ sọ́dọ̀ rẹ̀.+ 28 Wọ́n bọ́ aṣọ rẹ̀, wọ́n sì fi aṣọ ìlékè rírẹ̀dòdò kan bò ó lára,+ 29 wọ́n wá fi ẹ̀gún hun adé, wọ́n dé e sí i lórí, wọ́n sì fi ọ̀pá esùsú sí ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀. Wọ́n wá kúnlẹ̀ síwájú rẹ̀, wọ́n sì ń fi ṣe yẹ̀yẹ́, wọ́n ń sọ pé: “A kí ọ o,* ìwọ Ọba Àwọn Júù!” 30 Wọ́n tutọ́ sí i lára,+ wọ́n gba ọ̀pá esùsú náà, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í gbá a ní orí. 31 Níkẹyìn, lẹ́yìn tí wọ́n fi ṣe yẹ̀yẹ́, wọ́n bọ́ aṣọ ìlékè náà kúrò lára rẹ̀, wọ́n wá wọ aṣọ àwọ̀lékè rẹ̀ fún un, wọ́n sì mú un lọ kí wọ́n lè kàn án mọ́gi.+
32 Bí wọ́n ṣe ń jáde lọ, wọ́n rí ọkùnrin ará Kírénè kan tó ń jẹ́ Símónì. Wọ́n fi dandan mú ọkùnrin yìí pé kó gbé òpó igi oró* rẹ̀.+ 33 Nígbà tí wọ́n dé ibì kan tí wọ́n ń pè ní Gọ́gọ́tà, ìyẹn Ibi Agbárí,+ 34 wọ́n fún un ní wáìnì tí wọ́n pò mọ́ òróòro* mu;+ àmọ́ nígbà tó tọ́ ọ wò, ó kọ̀ láti mu ún. 35 Lẹ́yìn tí wọ́n kàn án mọ́gi, wọ́n fi kèké pín aṣọ àwọ̀lékè rẹ̀,+ 36 wọ́n sì jókòó síbẹ̀, wọ́n ń ṣọ́ ọ. 37 Wọ́n tún gbé àkọlé sókè orí rẹ̀, tí wọ́n kọ ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn án sí, pé: “Jésù Ọba Àwọn Júù nìyí.”+
38 Wọ́n wá kan àwọn olè méjì mọ́gi lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀, ọ̀kan ní ọ̀tún rẹ̀ àti ọ̀kan ní òsì rẹ̀.+ 39 Àwọn tó ń kọjá lọ ń bú u,+ wọ́n sì ń mi orí wọn,+ 40 wọ́n ń sọ pé: “Ìwọ tí o fẹ́ wó tẹ́ńpìlì palẹ̀, kí o sì fi ọjọ́ mẹ́ta kọ́ ọ,+ gba ara rẹ là! Tó bá jẹ́ pé ọmọ Ọlọ́run ni ọ́, sọ̀ kalẹ̀ lórí òpó igi oró!”*+ 41 Bákan náà, àwọn olórí àlùfáà àti àwọn akọ̀wé òfin pẹ̀lú àwọn àgbààgbà bẹ̀rẹ̀ sí í fi ṣe yẹ̀yẹ́, wọ́n ń sọ pé:+ 42 “Ó gba àwọn ẹlòmíì là; kò lè gba ara rẹ̀ là! Òun ni Ọba Ísírẹ́lì;+ kó sọ̀ kalẹ̀ báyìí látorí òpó igi oró,* a sì máa gbà á gbọ́. 43 Ó ti gbẹ́kẹ̀ lé Ọlọ́run; kí Ó gbà á sílẹ̀ báyìí tí Ó bá fẹ́ ẹ,+ torí ó sọ pé, ‘Ọmọ Ọlọ́run ni mí.’”+ 44 Bákan náà, àwọn olè tí wọ́n kàn mọ́gi lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀ pàápàá ń fi ṣe ẹlẹ́yà.+
45 Láti wákàtí kẹfà* lọ, òkùnkùn ṣú bo gbogbo ilẹ̀ náà, títí di wákàtí kẹsàn-án.*+ 46 Ní nǹkan bíi wákàtí kẹsàn-án, Jésù ké jáde pé: “Élì, Élì, làmá sàbákìtanì?” tó túmọ̀ sí, “Ọlọ́run mi, Ọlọ́run mi, kí ló dé tí o fi kọ̀ mí sílẹ̀?”+ 47 Nígbà tí àwọn kan lára àwọn tó dúró síbẹ̀ gbọ́ èyí, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í sọ pé: “Ọkùnrin yìí ń pe Èlíjà.”+ 48 Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, ọ̀kan lára wọn sáré lọ mú kànrìnkàn, ó sì rẹ ẹ́ sínú wáìnì kíkan, ó wá fi sórí ọ̀pá esùsú, ó sì fún un pé kó mu ún.+ 49 Àmọ́ àwọn yòókù sọ pé: “Ẹ fi sílẹ̀! Ká wò ó bóyá Èlíjà máa wá gbà á là.” 50 Jésù tún ké jáde, ó sì jọ̀wọ́ ẹ̀mí rẹ̀.*+
51 Wò ó! aṣọ ìdábùú ibi mímọ́+ ya sí méjì,+ látòkè dé ìsàlẹ̀,+ ilẹ̀ mì tìtì, àwọn àpáta sì là. 52 Àwọn ibojì* ṣí, ọ̀pọ̀ òkú àwọn ẹni mímọ́ tó ti sùn la sì gbé dìde, 53 (àwọn èèyàn tó ń jáde bọ̀ láti àárín àwọn ibojì lẹ́yìn tí a gbé e dìde wọnú ìlú mímọ́ náà), ọ̀pọ̀ èèyàn sì rí wọn. 54 Àmọ́ nígbà tí ọ̀gágun àti àwọn tó wà lọ́dọ̀ rẹ̀ tí wọ́n ń ṣọ́ Jésù rí bí ilẹ̀ ṣe mì tìtì àtàwọn ohun tó ń ṣẹlẹ̀, ẹ̀rù bà wọ́n gidigidi, wọ́n sì sọ pé: “Ó dájú pé Ọmọ Ọlọ́run nìyí.”+
55 Ọ̀pọ̀ àwọn obìnrin wà níbẹ̀ tí wọ́n ń wòran láti ọ̀ọ́kán, àwọn tó tẹ̀ lé Jésù wá láti Gálílì kí wọ́n lè ṣe ìránṣẹ́ fún un;+ 56 lára wọn ni Màríà Magidalénì, Màríà ìyá Jémíìsì àti Jósè àti ìyá àwọn ọmọ Sébédè.+
57 Bó ṣe ń di ọwọ́ ìrọ̀lẹ́, ọkùnrin ọlọ́rọ̀ kan tó jẹ́ ará Arimatíà dé, Jósẹ́fù lorúkọ rẹ̀, òun náà ti di ọmọ ẹ̀yìn Jésù.+ 58 Ọkùnrin yìí lọ bá Pílátù, ó sì ní kó gbé òkú Jésù fún òun.+ Pílátù wá pàṣẹ pé kí wọ́n gbé e fún un.+ 59 Jósẹ́fù gbé òkú náà, ó fi aṣọ ọ̀gbọ̀* tó dáa, tó sì mọ́ dì í,+ 60 ó sì tẹ́ ẹ sínú ibojì* rẹ̀ tuntun,+ èyí tó ti gbẹ́ sínú àpáta. Lẹ́yìn tó yí òkúta ńlá sí ẹnu ọ̀nà ibojì* náà, ó kúrò níbẹ̀. 61 Àmọ́ Màríà Magidalénì àti Màríà kejì ò kúrò níbẹ̀, wọ́n jókòó síwájú sàréè náà.+
62 Lọ́jọ́ kejì, lẹ́yìn Ìpalẹ̀mọ́,+ àwọn olórí àlùfáà àti àwọn Farisí kóra jọ síwájú Pílátù, 63 wọ́n sọ pé: “Ọ̀gá, a rántí ohun tí afàwọ̀rajà yẹn sọ nígbà tó ṣì wà láàyè, pé, ‘Lẹ́yìn ọjọ́ mẹ́ta, a máa jí mi dìde.’+ 64 Torí náà, pàṣẹ kí wọ́n sé sàréè náà mọ́ títí di ọjọ́ kẹta, kí àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ má bàa wá jí i gbé,+ kí wọ́n sì sọ fún àwọn èèyàn pé, ‘A ti jí i dìde!’ Ẹ̀tàn tó gbẹ̀yìn yìí máa wá burú ju ti àkọ́kọ́ lọ.” 65 Pílátù sọ fún wọn pé: “Ẹ mú ẹ̀ṣọ́. Ẹ lọ sé ibẹ̀ mọ́ bí ẹ bá ṣe lè ṣe é.” 66 Torí náà, wọ́n lọ sé sàréè náà mọ́, wọ́n gbé èdìdì lé òkúta náà, wọ́n sì fi ẹ̀ṣọ́ síbẹ̀.
28 Lẹ́yìn Sábáàtì, nígbà tí ilẹ̀ ń mọ́ bọ̀ ní ọjọ́ kìíní ọ̀sẹ̀, Màríà Magidalénì àti Màríà kejì wá wo sàréè náà.+
2 Wò ó! ìmìtìtì ilẹ̀ kan tó lágbára ti ṣẹlẹ̀, torí áńgẹ́lì Jèhófà* ti sọ̀ kalẹ̀ láti ọ̀run, ó ti wá yí òkúta náà kúrò, ó sì jókòó sórí rẹ̀.+ 3 Ìrísí rẹ̀ rí bíi mànàmáná, aṣọ rẹ̀ sì funfun bíi yìnyín.+ 4 Àní ẹ̀rù rẹ̀ ba àwọn ẹ̀ṣọ́ náà, jìnnìjìnnì bá wọn, wọ́n sì kú sára.
5 Àmọ́ áńgẹ́lì náà sọ fún àwọn obìnrin náà pé: “Ẹ má bẹ̀rù, torí mo mọ̀ pé Jésù tí wọ́n kàn mọ́gi lẹ̀ ń wá.+ 6 Kò sí níbí, torí a ti jí i dìde, bó ṣe sọ gẹ́lẹ́.+ Ẹ wá wo ibi tí wọ́n tẹ́ ẹ sí. 7 Kí ẹ tètè lọ sọ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé a ti jí i dìde, torí ẹ wò ó! ó ń lọ sí Gálílì ṣáájú yín.+ Ẹ máa rí i níbẹ̀. Ẹ wò ó! Mo ti sọ fún yín.”+
8 Torí náà, wọ́n yára kúrò ní ibojì ìrántí náà, bí ẹ̀rù ṣe ń bà wọ́n, tínú wọn sì ń dùn gan-an, wọ́n sáré lọ ròyìn fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀.+ 9 Wò ó! Jésù pàdé wọn, ó sì sọ pé: “Ẹ ǹlẹ́ o!” Wọ́n sún mọ́ ọn, wọ́n di ẹsẹ̀ rẹ̀ mú, wọ́n sì tẹrí ba* fún un. 10 Jésù wá sọ fún wọn pé: “Ẹ má bẹ̀rù! Ẹ lọ ròyìn fún àwọn arákùnrin mi, kí wọ́n lè lọ sí Gálílì, ibẹ̀ ni wọ́n ti máa rí mi.”
11 Bí wọ́n ṣe ń lọ, àwọn kan lára àwọn ẹ̀ṣọ́ náà+ lọ sínú ìlú, wọ́n sì ròyìn gbogbo ohun tó ṣẹlẹ̀ fún àwọn olórí àlùfáà. 12 Lẹ́yìn tí àwọn yìí kóra jọ pẹ̀lú àwọn àgbààgbà, tí wọ́n sì ti gbìmọ̀ pọ̀, wọ́n fún àwọn ọmọ ogun náà ní ẹyọ fàdákà tó pọ̀, 13 wọ́n sì sọ pé: “Kí ẹ sọ pé, ‘Àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ wá jí i gbé ní òru nígbà tí à ń sùn.’+ 14 Tí èyí bá sì dé etí gómìnà, a máa ṣàlàyé ọ̀rọ̀ náà fún un,* kò ní sídìí láti da ara yín láàmú.” 15 Torí náà, wọ́n gba àwọn ẹyọ fàdákà náà, wọ́n sì ṣe ohun tí wọ́n ní kí wọ́n ṣe, ọ̀rọ̀ yìí sì tàn káàkiri láàárín àwọn Júù títí dòní yìí.
16 Àmọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn mọ́kànlá (11) náà lọ sí Gálílì+ lórí òkè tí Jésù ṣètò pé kí wọ́n ti pàdé.+ 17 Nígbà tí wọ́n rí i, wọ́n tẹrí ba* fún un, àmọ́ àwọn kan ń ṣiyèméjì. 18 Jésù sún mọ́ wọn, ó sì sọ fún wọn pé: “Gbogbo àṣẹ ní ọ̀run àti ayé la ti fún mi.+ 19 Torí náà, ẹ lọ, kí ẹ máa sọ àwọn èèyàn gbogbo orílẹ̀-èdè di ọmọ ẹ̀yìn,+ ẹ máa batisí wọn+ ní orúkọ Baba àti ti Ọmọ àti ti ẹ̀mí mímọ́, 20 ẹ máa kọ́ wọn pé kí wọ́n máa pa gbogbo ohun tí mo pa láṣẹ fún yín mọ́.+ Ẹ wò ó! Mo wà pẹ̀lú yín ní gbogbo ọjọ́ títí dé ìparí ètò àwọn nǹkan.”*+
Tàbí “ìlà ìdílé.”
Tàbí “Mèsáyà; Ẹni Àmì Òróró.”
Tàbí “ipá ìṣiṣẹ́.”
Nínú ìgbà 237 tí a lo orúkọ náà, Jèhófà, nínú Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì, ibi àkọ́kọ́ nìyí tó ti fara hàn nínú ìtumọ̀ yìí. Wo Àfikún A5.
Tàbí “èyí tí o lóyún rẹ̀.”
Ìtumọ̀ kan náà ló ní pẹ̀lú orúkọ Hébérù náà, Jéṣúà tàbí Jóṣúà, tó túmọ̀ sí “Jèhófà Ni Ìgbàlà.”
Wo Àfikún A5.
Wo Àfikún A5.
Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.
Tàbí “onídán.”
Tàbí “tẹrí ba.”
Tàbí “Mèsáyà; Ẹni Àmì Òróró.”
Tàbí “tẹrí ba.”
Wo Àfikún A5.
Wo Àfikún A5.
Wo Àfikún A5.
Tàbí “ọkàn.”
Ó ṣeé ṣe kó wá látinú ọ̀rọ̀ Hébérù náà, “èéhù.”
Wo Àfikún A5.
Tàbí “ṣe batisí fún wọn.”
Tàbí “wíìtì.”
Ìyẹn, èèpo fúlẹ́fúlẹ́ ara ọkà.
Wo Àfikún A5.
Tàbí “ìgbátí; ibi tó ga jù ní.”
Wo Àfikún A5.
Wo Àfikún A5.
Tàbí “Agbègbè Tó Ní Ìlú Mẹ́wàá.”
Tàbí “àwọn tí àìní wọn nípa tẹ̀mí ń jẹ lọ́kàn; àwọn alágbe nípa tẹ̀mí.”
Tàbí “oníwà pẹ̀lẹ́.”
Tàbí “torí a máa tẹ́ wọn lọ́rùn.”
Tàbí “àwọn ẹlẹ́mìí àlàáfíà.”
Tàbí “apẹ̀rẹ̀ ìdíwọ̀n.”
Ibi tí wọ́n ti ń sun pàǹtírí lẹ́yìn odi Jerúsálẹ́mù. Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.
Ní Grk., “kúádíránì tó kù.” Wo Àfikún B14.
Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.
Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.
Lédè Gíríìkì, por·neiʹa. Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.
Wo Àfikún A5.
Ní Grk., “ẹ̀rẹ̀kẹ́.”
Wo Àfikún B14.
Ìyẹn, ẹni tó fẹ́ yá nǹkan láìsan èlé.
Tàbí “Kí ẹ pé pérépéré.”
Tàbí “ìtọrẹ fún àwọn aláìní.” Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.
Tàbí “kí a bọ̀wọ̀ fún orúkọ rẹ; kí a ka orúkọ rẹ sí mímọ́.”
Tàbí “dá wa nídè.”
Tàbí “wọn kì í túnra ṣe.”
Tàbí “kòkòrò.”
Tàbí “bá ríran kedere.”
Tàbí “kún fún ìmọ́lẹ̀.”
Ní Grk., “bá burú.”
Tàbí “ọkàn.”
Tàbí “ọkàn.”
Wo Àfikún B14.
Tàbí “ṣe òwú.”
Tàbí “tẹrí ba.”
Ní Grk., “rọ̀gbọ̀kú.”
Tàbí “tí ẹ̀ ń ṣojo.”
Tàbí “ibojì ìrántí.”
Tàbí “gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́.”
Tàbí “rọ̀gbọ̀kú nídìí tábìlì.”
Tàbí “rọ̀gbọ̀kú nídìí tábìlì.”
Tàbí “tẹrí ba.”
Tàbí “onítara.”
Tàbí “aṣọ míì.”
Tàbí “tó fara dà á.”
Orúkọ tí wọ́n ń pe Sátánì, olórí tàbí alákòóso àwọn ẹ̀mí èṣù.
Tàbí “ẹ̀mí,” ìyẹn, ìrètí láti tún wà láàyè.
Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.
Ní Grk., “Ásáríò kan.” Wo Àfikún B14.
Tàbí “fò wá sílẹ̀.”
Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.
Tàbí “ẹ̀mí.”
Tàbí “ẹ̀mí.”
Ìyẹn, koríko etí omi.
Ní Grk., “aṣọ múlọ́múlọ́.”
Ní Grk., “síwájú ojú rẹ.”
Tàbí “a dá ọgbọ́n láre.”
Tàbí “àwọn èso rẹ̀.”
Ní Grk., “aṣọ àpò ìdọ̀họ.”
Tàbí “Hédíìsì,” ìyẹn ibojì aráyé. Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.
Tàbí “tu ọkàn yín.”
Tàbí “jẹ́ ti inú rere.”
Ìyẹn, orí ọkà.
Tàbí “búrẹ́dì àfihàn.”
Tàbí “ọkàn mi.”
Ìyẹn, koríko etí omi.
Orúkọ tí wọ́n ń pe Sátánì.
Tàbí “àsìkò yìí.” Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.
Tàbí “aláìṣòótọ́.”
Ní Grk., “ọ̀sán mẹ́ta àti òru mẹ́ta.”
Tàbí “àsìkò yìí.” Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.
Tàbí “wíìtì.”
Tàbí kó jẹ́, “láti ìgbà tí a ti fi ìpìlẹ̀ ayé sọlẹ̀.”
Tàbí “àsìkò kan.” Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.
Tàbí “àsìkò náà.” Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.
Tàbí “àsìkò náà.” Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.
Ní Grk., “alákòóso ìdá mẹ́rin.”
Ìyẹn, Hẹ́rọ́dù Áńtípà. Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.
Tàbí “àwọn tó rọ̀gbọ̀kú sídìí tábìlì pẹ̀lú rẹ̀.”
Tàbí “rọ̀gbọ̀kú.”
Ní Grk., “ọ̀pọ̀ sítédíọ̀mù.” Sítédíọ̀mù kan jẹ́ mítà 185 (606.95 ẹsẹ̀ bàtà).
Ìyẹn, nǹkan bí aago mẹ́ta òru títí dìgbà tí ilẹ̀ mọ́ ní nǹkan bí aago mẹ́fà àárọ̀.
Tàbí “forí balẹ̀.”
Ìyẹn, àṣà ìwẹ̀mọ́.
Tàbí “kẹ́gàn.”
Ó ń tọ́ka sí ọ̀rọ̀ Gíríìkì náà, por·neiʹa tí wọ́n bá lò ó fún ohun tó ju ẹyọ kan lọ. Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.
Ìyẹn, tí kò bá tẹ̀ lé àṣà ìwẹ̀mọ́.
Tàbí “forí balẹ̀.”
Tàbí “pẹ̀lú ebi.”
Tàbí “rọ̀gbọ̀kú sórí ilẹ̀.”
Tàbí “apẹ̀rẹ̀ ìkẹ́rùsí.”
Tàbí “aláìṣòótọ́.”
Tàbí “apẹ̀rẹ̀ ìkẹ́rùsí.”
Tàbí “torí pé èèyàn.”
Tàbí “Hédíìsì,” ìyẹn ibojì aráyé. Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.
Ní Grk., “Bọ́ sẹ́yìn mi.”
Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.
Tàbí “ọkàn.”
Tàbí “ọkàn.”
Tàbí “ọkàn.”
Tàbí “ọkàn.”
Tàbí “funfun.”
Tàbí “àwọsánmà.”
Wo Àfikún A3.
Ní Grk., “dírákímà méjì alápapọ̀.” Wo Àfikún B14.
Ní Grk., “ẹyọ owó sítátà kan,” òun ni wọ́n kà sí dírákímà mẹ́rin alápapọ̀. Wo Àfikún B14.
Tàbí “yíwà pa dà.”
Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.
Wo Àfikún A3.
Tàbí kó jẹ́, “yín.”
Ní Grk., “lọ bá a wí.”
Ní Grk., “láti ẹnu.”
10,000 tálẹ́ńtì fàdákà jẹ́ 60,000,000 owó dínárì. Wo Àfikún B14.
Tàbí “tẹrí ba.”
Wo Àfikún B14.
Lédè Gíríìkì, por·neiʹa. Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.
Tàbí “pé pérépéré.”
Wo Àfikún B14.
Ìyẹn, nǹkan bí aago mẹ́sàn-án àárọ̀.
Ìyẹn, nǹkan bí aago méjìlá ọ̀sán.
Ìyẹn, nǹkan bí aago mẹ́ta ọ̀sán.
Ìyẹn, nǹkan bí aago márùn-ún ìrọ̀lẹ́.
Wo Àfikún B14.
Wo Àfikún B14.
Wo Àfikún B14.
Ní Grk., “burú.”
Tàbí “jẹ́ ọ̀làwọ́.”
Tàbí “forí balẹ̀.”
Tàbí “ọkàn.”
Tàbí “agódóńgbó.”
Wo Àfikún A5.
Tàbí “ó pilẹ̀ṣẹ̀ látọ̀dọ̀ èèyàn?”
Tàbí “burú.”
Ní Grk., “olórí igun.”
Wo Àfikún A5.
Tàbí “fàṣẹ ọba mú un.”
Tàbí “àwọn tó rọ̀gbọ̀kú sídìí tábìlì.”
Tàbí “tọ́.”
Wo Àfikún B14.
Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀, “Ọkàn.”
Wo Àfikún A5.
Wo Àfikún A5.
Tàbí “wọ́n fẹ àwọn akóló wọn.”
Tàbí “tó dáa jù.”
Tàbí “Olùkọ́.”
Wo Àfikún A3.
Ìyẹn, “ẹni tó gba ẹ̀sìn Júù.” Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.
Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.
Tàbí “kòkòrò abìyẹ́ tó ń mùjẹ̀.”
Tàbí “ìkónilẹ́rù.”
Tàbí “ibojì ìrántí.”
Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.
Tàbí “mọ́ òpó igi.” Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.
Tàbí kó jẹ́, “fi ilé yín sílẹ̀ fún yín ní ahoro.”
Wo Àfikún A5.
Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀, “Wíwàníhìn-ín.”
Tàbí “àsìkò náà.” Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.
Tàbí “tó fara dà á.”
Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀, “Wíwàníhìn-ín.”
Tàbí “ìkùukùu.”
Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀, “Wíwàníhìn-ín.”
Tàbí “àkókò tí olè ń bọ̀ ní òru.”
Tàbí “ọlọ́gbọ́n.”
Tàbí “ọlọ́gbọ́n.”
Tàbí “kòlòbó.”
Tálẹ́ńtì ilẹ̀ Gíríìkì kan jẹ́ 20.4 kìlógíráàmù. Wo Àfikún B14.
Ní Grk., “fàdákà.”
Ní Grk., “fàdákà.”
Tàbí “aṣọ ò bò mí lára dáadáa.”
Ìyẹn, ìkékúrò nínú ìyè. Ní Grk., “gé kúrò; rẹ́ kúrò.”
Tàbí “ẹ̀tàn.”
Tàbí “fàṣẹ ọba mú.”
Tàbí “ìgò.”
Tàbí “rọ̀gbọ̀kú nídìí tábìlì.”
Tàbí “rọ̀gbọ̀kú.”
Tàbí “kọ orin ìjọsìn; kọ sáàmù.”
Tàbí “bá ọkàn mi.”
Tàbí “ó wu ẹ̀mí.”
Tàbí “ìwé mímọ́.”
Tàbí “ìkùukùu.”
Tàbí “bí o ṣe ń sọ̀rọ̀.”
Tàbí “Wàhálà tìẹ nìyẹn!”
Wo Àfikún A5.
Tàbí “mọ́ òpó igi.” Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.
Tàbí “A júbà rẹ.”
Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.
Ohun mímu tó korò.
Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.
Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.
Ìyẹn, nǹkan bí aago méjìlá ọ̀sán.
Ìyẹn, nǹkan bí aago mẹ́ta ọ̀sán.
Tàbí “ó sì gbẹ́mìí mì.”
Tàbí “ibojì ìrántí.”
Tàbí “aṣọ àtàtà.”
Tàbí “ibojì ìrántí.”
Tàbí “ibojì ìrántí.”
Wo Àfikún A5.
Tàbí “forí balẹ̀.”
Ní Grk., “yí i lérò pa dà.”
Tàbí “forí balẹ̀.”
Tàbí “àsìkò náà.” Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.