LÉFÍTÍKÙ
1 Jèhófà pe Mósè, ó sì bá a sọ̀rọ̀ látinú àgọ́ ìpàdé,+ pé: 2 “Bá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì* sọ̀rọ̀, kí o sì sọ fún wọn pé, ‘Tí ẹnikẹ́ni nínú yín bá fẹ́ fi ẹran ọ̀sìn ṣe ọrẹ fún Jèhófà, kó mú ọrẹ rẹ̀ wá látinú ọ̀wọ́ ẹran tàbí agbo ẹran.+
3 “‘Tó bá fẹ́ mú ẹran wá láti fi rú ẹbọ sísun látinú ọ̀wọ́ ẹran, kó jẹ́ akọ tí ara rẹ̀ dá ṣáṣá.+ Tinútinú+ ni kó mú un wá síwájú Jèhófà ní ẹnu ọ̀nà àgọ́ ìpàdé. 4 Kó gbé ọwọ́ rẹ̀ lé orí ẹran náà, ọrẹ rẹ̀ yóò sì ní ìtẹ́wọ́gbà, á sì jẹ́ ètùtù fún un.
5 “‘Lẹ́yìn náà, kí wọ́n pa akọ màlúù náà níwájú Jèhófà, àwọn ọmọ Áárónì, tí wọ́n jẹ́ àlùfáà,+ yóò sì gbé ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ wá, wọ́n á wọ́n ọn sí gbogbo ẹ̀gbẹ́ pẹpẹ náà,+ èyí tó wà ní ẹnu ọ̀nà àgọ́ ìpàdé. 6 Kí wọ́n bó awọ ẹran náà, kí wọ́n sì gé e sí wẹ́wẹ́.+ 7 Kí àwọn ọmọ Áárónì, tí wọ́n jẹ́ àlùfáà, dá iná sórí pẹpẹ,+ kí wọ́n sì to igi sí iná náà. 8 Kí àwọn ọmọ Áárónì, tí wọ́n jẹ́ àlùfáà, to àwọn ègé ẹran náà+ sórí igi tó wà lórí iná lórí pẹpẹ, pẹ̀lú orí rẹ̀ àti ọ̀rá rẹ̀ líle.* 9 Kí wọ́n fi omi fọ ìfun rẹ̀ àti ẹsẹ̀ rẹ̀, kí àlùfáà sì mú kí gbogbo rẹ̀ rú èéfín lórí pẹpẹ gẹ́gẹ́ bí ẹbọ sísun, ọrẹ àfinásun sí Jèhófà, tó ní òórùn dídùn.*+
10 “‘Tó bá fẹ́ mú ẹran wá láti fi rú ẹbọ sísun látinú agbo ẹran,+ lára àwọn ọmọ àgbò tàbí àwọn ewúrẹ́, kó jẹ́ akọ tí ara rẹ̀ dá ṣáṣá.+ 11 Kí wọ́n pa á ní apá àríwá pẹpẹ níwájú Jèhófà, kí àwọn ọmọ Áárónì, tí wọ́n jẹ́ àlùfáà, sì wọ́n ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ sí gbogbo ẹ̀gbẹ́ pẹpẹ.+ 12 Kó gé e sí wẹ́wẹ́, kó gé orí rẹ̀ àti ọ̀rá rẹ̀ líle,* kí àlùfáà sì tò ó sórí igi tó wà lórí iná lórí pẹpẹ. 13 Kó fi omi fọ ìfun àti ẹsẹ̀ rẹ̀, kí àlùfáà sì mú gbogbo rẹ̀ wá, kó sun ún lórí pẹpẹ kó lè rú èéfín. Ẹbọ sísun ni, ọrẹ àfinásun sí Jèhófà, tó ní òórùn dídùn.*
14 “‘Àmọ́ tó bá jẹ́ pé ẹyẹ ló fẹ́ mú wá láti fi rú ẹbọ sísun sí Jèhófà, kó mú ọrẹ rẹ̀ wá látinú àwọn ẹyẹ oriri tàbí ọmọ ẹyẹlé.+ 15 Kí àlùfáà sì mú un wá síbi pẹpẹ, kó já ọrùn rẹ̀ láìjá a tán, kó sì mú kó rú èéfín lórí pẹpẹ, àmọ́ kó ro ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ sí ẹ̀gbẹ́ pẹpẹ. 16 Kó yọ àpò oúnjẹ ẹyẹ náà, kó tu àwọn ìyẹ́ rẹ̀, kó sì jù wọ́n sẹ́gbẹ̀ẹ́ pẹpẹ lápá ìlà oòrùn, níbi tí eérú*+ wà. 17 Kó là á níbi àwọn ìyẹ́ rẹ̀ láìgé e sí méjì. Lẹ́yìn náà, kí àlùfáà mú kó rú èéfín lórí igi tó wà lórí iná lórí pẹpẹ. Ẹbọ sísun ni, ọrẹ àfinásun sí Jèhófà, tó ní òórùn dídùn.*
2 “‘Tí ẹnì* kan bá fẹ́ mú ọrẹ ọkà+ wá fún Jèhófà, kó jẹ́ ìyẹ̀fun tó kúnná, kó da òróró sórí rẹ̀, kó sì fi oje igi tùràrí sórí rẹ̀.+ 2 Kó wá gbé e wá fún àwọn ọmọ Áárónì, tí wọ́n jẹ́ àlùfáà, kí àlùfáà sì bu ẹ̀kúnwọ́ ìyẹ̀fun náà tí wọ́n pò mọ́ òróró àti gbogbo oje igi tùràrí rẹ̀, kó sì mú kó rú èéfín lórí pẹpẹ bí ọrẹ ìṣàpẹẹrẹ,*+ ọrẹ àfinásun sí Jèhófà, tó ní òórùn dídùn.* 3 Kí ohunkóhun tó bá ṣẹ́ kù lára ọrẹ ọkà náà jẹ́ ti Áárónì àti àwọn ọmọ rẹ̀,+ ohun mímọ́ jù lọ ló jẹ́+ látinú àwọn ọrẹ àfinásun sí Jèhófà.
4 “‘Tí o bá fẹ́ fi ohun tí wọ́n yan nínú ààrò ṣe ọrẹ ọkà, kó jẹ́ èyí tí wọ́n fi ìyẹ̀fun tó kúnná ṣe, búrẹ́dì aláìwú tí wọ́n fi òróró pò, tó rí bí òrùka tàbí búrẹ́dì aláìwú pẹlẹbẹ tí wọ́n fi òróró pa.+
5 “‘Tó bá jẹ́ ohun tí wọ́n ṣe nínú agbada+ lo fẹ́ fi ṣe ọrẹ ọkà, kó jẹ́ èyí tí wọ́n fi ìyẹ̀fun tó kúnná ṣe, tí wọ́n pò mọ́ òróró, tí kò sì ní ìwúkàrà. 6 Kí o gé e sí wẹ́wẹ́, kí o sì da òróró sórí rẹ̀.+ Ọrẹ ọkà ni.
7 “‘Tó bá jẹ́ ohun tí wọ́n sè nínú páànù lo fẹ́ fi ṣe ọrẹ ọkà, kó jẹ́ èyí tí wọ́n fi ìyẹ̀fun tó kúnná pẹ̀lú òróró ṣe. 8 Àwọn nǹkan yìí ni kí o fi ṣe ọrẹ ọkà tí o máa mú wá fún Jèhófà, kí o gbé e fún àlùfáà, yóò sì gbé e sún mọ́ pẹpẹ. 9 Kí àlùfáà mú lára ọrẹ ọkà náà láti fi ṣe ọrẹ ìṣàpẹẹrẹ,*+ kó mú kó rú èéfín lórí pẹpẹ bí ọrẹ àfinásun tó ní òórùn dídùn* sí Jèhófà.+ 10 Kí ohun tó bá ṣẹ́ kù lára ọrẹ ọkà náà jẹ́ ti Áárónì àti àwọn ọmọ rẹ̀, ohun mímọ́ jù lọ ló jẹ́ látinú àwọn ọrẹ àfinásun+ sí Jèhófà.
11 “‘Ẹ má ṣe mú ọrẹ ọkà kankan tó ní ìwúkàrà+ wá fún Jèhófà, ẹ ò sì gbọ́dọ̀ mú kí àpòrọ́ kíkan tàbí oyin èyíkéyìí rú èéfín bí ọrẹ àfinásun sí Jèhófà.
12 “‘Ẹ lè mú wọn wá fún Jèhófà láti fi ṣe ọrẹ àwọn àkọ́so+ yín, àmọ́ ẹ má ṣe mú un wá sórí pẹpẹ láti mú òórùn dídùn* jáde.
13 “‘Kí ẹ fi iyọ̀ dun gbogbo ọrẹ ọkà tí ẹ bá mú wá; ẹ ò gbọ́dọ̀ jẹ́ kí iyọ̀ májẹ̀mú Ọlọ́run yín di àwátì nínú ọrẹ ọkà yín. Kí ẹ máa fi iyọ̀+ sí gbogbo ọrẹ yín.
14 “‘Tí o bá fẹ́ ṣe ọrẹ ọkà àkọ́pọ́n èso rẹ fún Jèhófà, ọkà tuntun* tí o yan lórí iná ni kí o mú wá, kóró tuntun tí o kò lọ̀ kúnná, kí o fi ṣe ọrẹ ọkà àkọ́pọ́n èso+ rẹ. 15 Kí o da òróró sórí rẹ̀, kí o sì fi oje igi tùràrí sórí rẹ̀. Ọrẹ ọkà ni. 16 Kí àlùfáà mú kó rú èéfín bí ọrẹ ìṣàpẹẹrẹ,*+ ìyẹn, díẹ̀ lára ọkà tí ẹ kò lọ̀ kúnná àti òróró pẹ̀lú gbogbo oje igi tùràrí rẹ̀, kó fi ṣe ọrẹ àfinásun sí Jèhófà.
3 “‘Tí ohun tó mú wá bá jẹ́ ẹbọ ìrẹ́pọ̀,*+ tó sì jẹ́ látinú ọ̀wọ́ ẹran ló ti fẹ́ mú un wá, yálà akọ tàbí abo, ẹran tí ara rẹ̀ dá ṣáṣá ni kó mú wá fún Jèhófà. 2 Kó gbé ọwọ́ lé orí ẹran tó mú wá, kí wọ́n pa á ní ẹnu ọ̀nà àgọ́ ìpàdé; kí àwọn ọmọ Áárónì, àwọn àlùfáà, sì wọ́n ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ sí gbogbo ẹ̀gbẹ́ pẹpẹ. 3 Kó fi lára ẹbọ ìrẹ́pọ̀ náà ṣe ọrẹ àfinásun sí Jèhófà:+ ọ̀rá+ tó bo ìfun, gbogbo ọ̀rá tó yí ìfun ká 4 àti kíndìnrín méjèèjì pẹ̀lú ọ̀rá tó wà lára wọn nítòsí abẹ́nú rẹ̀. Kó tún yọ àmọ́ tó wà lára ẹ̀dọ̀, pẹ̀lú àwọn kíndìnrín+ ẹran náà. 5 Kí àwọn ọmọ Áárónì mú kó rú èéfín lórí pẹpẹ, lórí ẹbọ sísun tó wà lórí igi lórí iná;+ ọrẹ àfinásun tó ní òórùn dídùn* ló jẹ́ sí Jèhófà.+
6 “‘Tó bá jẹ́ látinú agbo ẹran ló ti fẹ́ mú ọrẹ wá fún Jèhófà láti fi rú ẹbọ ìrẹ́pọ̀, kó jẹ́ akọ tàbí abo tí ara rẹ̀ dá ṣáṣá.+ 7 Tó bá jẹ́ ọmọ àgbò ló fẹ́ fi ṣe ọrẹ, kó mú un wá síwájú Jèhófà. 8 Kó gbé ọwọ́ lé orí ẹran tó mú wá, kí wọ́n sì pa á níwájú àgọ́ ìpàdé. Kí àwọn ọmọ Áárónì wọ́n ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ sí gbogbo ẹ̀gbẹ́ pẹpẹ. 9 Kó mú ọ̀rá látinú ẹbọ ìrẹ́pọ̀, kó fi ṣe ọrẹ àfinásun sí Jèhófà.+ Kó gé ìrù rẹ̀ tó lọ́ràá nítòsí eegun ẹ̀yìn kúrò lódindi, ọ̀rá tó bo ìfun, gbogbo ọ̀rá tó yí ìfun ká, 10 pẹ̀lú kíndìnrín méjèèjì àti ọ̀rá tó wà lára wọn nítòsí abẹ́nú. Kó tún yọ àmọ́ tó wà lára ẹ̀dọ̀ pẹ̀lú àwọn kíndìnrín+ náà. 11 Kí àlùfáà mú kó rú èéfín lórí pẹpẹ bí oúnjẹ,* ọrẹ àfinásun sí Jèhófà+ ló jẹ́.
12 “‘Tó bá jẹ́ ewúrẹ́ ló fẹ́ fi ṣe ọrẹ, kó mú un wá síwájú Jèhófà. 13 Kó gbé ọwọ́ lé e lórí, kí wọ́n pa á níwájú àgọ́ ìpàdé, kí àwọn ọmọ Áárónì sì wọ́n ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ sí gbogbo ẹ̀gbẹ́ pẹpẹ. 14 Ibi tó máa fi ṣe ọrẹ àfinásun sí Jèhófà lára ẹran náà ni ọ̀rá tó bo ìfun, gbogbo ọ̀rá tó yí ìfun ká,+ 15 pẹ̀lú kíndìnrín méjèèjì àti ọ̀rá tó wà lára wọn nítòsí abẹ́nú. Kó tún yọ àmọ́ tó wà lára ẹ̀dọ̀ pẹ̀lú àwọn kíndìnrín rẹ̀. 16 Kí àlùfáà mú kó rú èéfín lórí pẹpẹ bí oúnjẹ, ọrẹ àfinásun tó máa mú òórùn dídùn* jáde ló jẹ́. Ti Jèhófà ni gbogbo ọ̀rá.+
17 “‘Ó jẹ́ àṣẹ tó máa wà fún àwọn ìran yín títí lọ, ní gbogbo ibi tí ẹ̀ ń gbé: Ẹ ò gbọ́dọ̀ jẹ ọ̀rá tàbí ẹ̀jẹ̀+ èyíkéyìí.’”
4 Jèhófà wá sọ fún Mósè pé: 2 “Sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé, ‘Tí ẹnì* kan bá ṣẹ̀ láìmọ̀ọ́mọ̀,+ tó ṣe èyíkéyìí nínú ohun tí Jèhófà pa láṣẹ pé kí ẹ má ṣe:
3 “‘Tí àlùfáà tí ẹ fòróró yàn+ bá dẹ́ṣẹ̀,+ tó sì mú kí àwọn èèyàn jẹ̀bi, kó mú akọ ọmọ màlúù kan tí ara rẹ̀ dá ṣáṣá wá fún Jèhófà, kó fi rú ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ fún ẹ̀ṣẹ̀ tó dá.+ 4 Kó mú akọ màlúù náà wá sí ẹnu ọ̀nà àgọ́ ìpàdé+ níwájú Jèhófà, kó gbé ọwọ́ rẹ̀ lé orí akọ màlúù náà, kó sì pa á níwájú Jèhófà.+ 5 Kí àlùfáà tí ẹ fòróró yàn+ náà wá mú lára ẹ̀jẹ̀ akọ màlúù náà, kó sì gbé e wá sínú àgọ́ ìpàdé; 6 kí àlùfáà náà ki ìka rẹ̀ bọ ẹ̀jẹ̀ náà,+ kó sì wọ́n lára ẹ̀jẹ̀ náà lẹ́ẹ̀méje+ níwájú Jèhófà, síwájú aṣọ ìdábùú ibi mímọ́. 7 Kí àlùfáà náà tún fi lára ẹ̀jẹ̀ náà sí ara àwọn ìwo pẹpẹ tùràrí onílọ́fínńdà,+ tó wà níwájú Jèhófà nínú àgọ́ ìpàdé; kó sì da gbogbo ìyókù ẹ̀jẹ̀ akọ màlúù náà sí ìsàlẹ̀ pẹpẹ ẹbọ sísun,+ tó wà ní ẹnu ọ̀nà àgọ́ ìpàdé.
8 “‘Lẹ́yìn náà, kó yọ gbogbo ọ̀rá tó wà lára akọ màlúù ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ náà, títí kan ọ̀rá tó bo ìfun àti ọ̀rá tó yí ìfun ká 9 àti kíndìnrín méjèèjì pẹ̀lú ọ̀rá tó wà lára wọn nítòsí abẹ́nú. Kó yọ àmọ́ tó wà lára ẹ̀dọ̀, pẹ̀lú àwọn kíndìnrín+ rẹ̀. 10 Ohun kan náà tó yọ lára akọ màlúù ẹbọ ìrẹ́pọ̀+ ni kó yọ. Kí àlùfáà sì mú kó rú èéfín lórí pẹpẹ ẹbọ sísun.
11 “‘Àmọ́ ní ti awọ akọ màlúù náà àti gbogbo ẹran rẹ̀ pẹ̀lú orí, ẹsẹ̀, ìfun àti ìgbẹ́+ rẹ̀, 12 gbogbo ohun tó kù lára akọ màlúù náà, kí ó kó o lọ sí ẹ̀yìn ibùdó níbi tó mọ́, tí wọ́n ń da eérú* sí, kó sì sun ún lórí igi nínú iná.+ Ibi tí wọ́n ń da eérú sí ni kó ti sun ún.
13 “‘Tó bá wá ṣẹlẹ̀ pé gbogbo àpéjọ Ísírẹ́lì dẹ́ṣẹ̀ láìmọ̀ọ́mọ̀,+ tí wọ́n sì jẹ̀bi, àmọ́ tí gbogbo ìjọ ò mọ̀ pé àwọn ti ṣe ohun tí Jèhófà pa láṣẹ pé kí wọ́n má ṣe,+ 14 tí wọ́n bá wá mọ̀ pé wọ́n dẹ́ṣẹ̀, kí ìjọ mú akọ ọmọ màlúù kan wá láti fi rú ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, kí wọ́n sì mú un wá síwájú àgọ́ ìpàdé. 15 Kí àwọn àgbààgbà àpéjọ náà gbé ọwọ́ wọn lé orí akọ màlúù náà níwájú Jèhófà, kí wọ́n sì pa akọ màlúù náà níwájú Jèhófà.
16 “‘Lẹ́yìn náà, kí àlùfáà tí ẹ fòróró yàn mú lára ẹ̀jẹ̀ akọ màlúù náà wá sínú àgọ́ ìpàdé. 17 Kí àlùfáà náà ki ìka rẹ̀ bọnú ẹ̀jẹ̀ náà, kó sì wọ́n lára rẹ̀ lẹ́ẹ̀méje níwájú Jèhófà, síwájú aṣọ ìdábùú.+ 18 Kó wá fi lára ẹ̀jẹ̀ náà sára àwọn ìwo pẹpẹ+ tó wà níwájú Jèhófà, èyí tó wà nínú àgọ́ ìpàdé; kó sì da gbogbo ẹ̀jẹ̀ tó kù sí ìsàlẹ̀ pẹpẹ ẹbọ sísun, tó wà ní ẹnu ọ̀nà àgọ́ ìpàdé.+ 19 Kó yọ gbogbo ọ̀rá rẹ̀, kó sì mú kó rú èéfín lórí pẹpẹ.+ 20 Ohun tó ṣe sí akọ màlúù kejì tó jẹ́ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ ni kó ṣe sí akọ màlúù náà. Bó ṣe máa ṣe é nìyẹn, kí àlùfáà ṣe ètùtù fún wọn,+ wọ́n á sì rí ìdáríjì. 21 Kó mú akọ màlúù náà lọ sí ẹ̀yìn ibùdó, kó sì sun ún, bó ṣe sun akọ màlúù àkọ́kọ́.+ Ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ fún ìjọ+ ni.
22 “‘Tí ìjòyè+ kan bá ṣẹ̀ láìmọ̀ọ́mọ̀, tó ṣe ọ̀kan nínú gbogbo ohun tí Jèhófà Ọlọ́run rẹ̀ pa láṣẹ pé kí ẹ má ṣe, tí ìjòyè náà sì jẹ̀bi, 23 tàbí tó wá mọ̀ pé òun ti ṣe ohun tó lòdì sí àṣẹ náà, kó mú akọ ọmọ ewúrẹ́ tí ara rẹ̀ dá ṣáṣá wá láti fi ṣe ọrẹ. 24 Kó gbé ọwọ́ rẹ̀ lé orí ọmọ ewúrẹ́ náà, kó sì pa á níbi tí wọ́n ti ń pa ẹran ẹbọ sísun níwájú Jèhófà.+ Ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ ni. 25 Kí àlùfáà fi ìka rẹ̀ mú lára ẹ̀jẹ̀ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ náà, kó fi sára àwọn ìwo+ pẹpẹ ẹbọ sísun, kó sì da ẹ̀jẹ̀ tó kù sí ìsàlẹ̀ pẹpẹ ẹbọ sísun.+ 26 Kó mú kí gbogbo ọ̀rá rẹ̀ rú èéfín lórí pẹpẹ bí ọ̀rá ẹbọ ìrẹ́pọ̀;+ àlùfáà yóò sì ṣe ètùtù fún un torí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, yóò sì rí ìdáríjì.
27 “‘Tí ẹnì* kankan nínú àwọn èèyàn ilẹ̀ náà bá ṣẹ̀ láìmọ̀ọ́mọ̀, tó ṣe ọ̀kan nínú àwọn ohun tí Jèhófà pa láṣẹ pé kí ẹ má ṣe,+ tí ẹni náà sì jẹ̀bi, 28 tàbí tó wá mọ̀ pé òun ti ṣẹ̀, kó mú abo ọmọ ewúrẹ́ tí ara rẹ̀ dá ṣáṣá wá láti fi rú ẹbọ torí ẹ̀ṣẹ̀ tó dá. 29 Kó gbé ọwọ́ rẹ̀ lé orí ẹran ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, kó sì pa á ní ibì kan náà tó ti pa ẹran ẹbọ sísun.+ 30 Kí àlùfáà fi ìka rẹ̀ mú lára ẹ̀jẹ̀ rẹ̀, kó fi sára àwọn ìwo pẹpẹ ẹbọ sísun, kó sì da gbogbo ẹ̀jẹ̀ tó kù sí ìsàlẹ̀ pẹpẹ.+ 31 Kó yọ gbogbo ọ̀rá+ rẹ̀, bó ṣe yọ ọ̀rá kúrò lára ẹran ẹbọ ìrẹ́pọ̀,+ kí àlùfáà sì mú kó rú èéfín lórí pẹpẹ láti mú òórùn dídùn* jáde sí Jèhófà; kí àlùfáà ṣe ètùtù fún un, yóò sì rí ìdáríjì.
32 “‘Àmọ́ tó bá jẹ́ ọ̀dọ́ àgùntàn ló fẹ́ mú wá láti fi rú ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, abo ọ̀dọ́ àgùntàn tí ara rẹ̀ dá ṣáṣá ni kó mú wá. 33 Kó gbé ọwọ́ rẹ̀ lé orí ẹran ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ náà, kó sì pa á bí ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ níbi tí wọ́n ti ń pa ẹran ẹbọ sísun.+ 34 Kí àlùfáà fi ìka rẹ̀ mú lára ẹ̀jẹ̀ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ náà, kó fi sára àwọn ìwo pẹpẹ ẹbọ sísun,+ kó sì da gbogbo ẹ̀jẹ̀ tó kù sí ìsàlẹ̀ pẹpẹ. 35 Kó yọ gbogbo ọ̀rá rẹ̀ bí wọ́n ṣe ń yọ ọ̀rá ọmọ àgbò tí wọ́n fi ṣe ẹbọ ìrẹ́pọ̀, kí àlùfáà sì mú kó rú èéfín lórí pẹpẹ, lórí àwọn ọrẹ àfinásun sí Jèhófà;+ kí àlùfáà sì ṣe ètùtù fún un torí ẹ̀ṣẹ̀ tó dá, yóò sì rí ìdáríjì.+
5 “‘Tí ẹnì* kan bá gbọ́ tí wọ́n ń kéde ní gbangba pé kí ẹni tó bá mọ̀ nípa ọ̀rọ̀ kan wá jẹ́rìí sí i,*+ tí ẹni náà sì jẹ́ ẹlẹ́rìí ọ̀rọ̀ náà tàbí tó ṣojú rẹ̀ tàbí tó mọ̀ nípa rẹ̀, àmọ́ tí kò sọ, ó ti ṣẹ̀, yóò sì jìyà ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀.
2 “‘Tàbí tí ẹnì* kan bá fara kan ohun àìmọ́ èyíkéyìí, yálà òkú ẹran inú igbó tó jẹ́ aláìmọ́, ẹran ọ̀sìn tó jẹ́ aláìmọ́ tàbí ọ̀kan lára àwọn ohun alààyè tó ń gbá yìn-ìn tó jẹ́ aláìmọ́,+ ẹni náà máa di aláìmọ́, á sì jẹ̀bi, kódà tí kò bá tiẹ̀ mọ̀. 3 Tó bá sì ṣẹlẹ̀ pé ẹnì kan fara kan ohun àìmọ́ ti èèyàn+ láìmọ̀, ohun àìmọ́ èyíkéyìí tó lè sọ ọ́ di aláìmọ́, tó sì wá mọ̀, ó ti jẹ̀bi.
4 “‘Tàbí tí ẹnì* kan bá búra láìronú jinlẹ̀ pé òun máa ṣe ohun kan, yálà ohun tó dáa tàbí ohun tí kò dáa, ohun yòówù kó jẹ́, tí kò sì mọ̀, àmọ́ tó wá mọ̀ pé òun ti búra láìronú jinlẹ̀, ó ti jẹ̀bi.*+
5 “‘Tó bá jẹ̀bi torí pé ó ṣe ọ̀kan nínú àwọn nǹkan yìí, kó jẹ́wọ́+ èyí tó ṣe gan-an. 6 Kó tún mú ẹbọ ẹ̀bi rẹ̀ wá fún Jèhófà torí ẹ̀ṣẹ̀ tó dá,+ ìyẹn abo ẹran látinú agbo ẹran láti fi rú ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, ó lè jẹ́ abo ọ̀dọ́ àgùntàn tàbí abo ọmọ ewúrẹ́. Àlùfáà yóò wá ṣe ètùtù fún un torí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀.
7 “‘Àmọ́ tí agbára rẹ̀ ò bá gbé àgùntàn, kó mú ẹyẹ oriri méjì tàbí ọmọ ẹyẹlé méjì+ wá fún Jèhófà láti fi rú ẹbọ ẹ̀bi fún ẹ̀ṣẹ̀ tó dá, ọ̀kan fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, ìkejì fún ẹbọ sísun.+ 8 Kó mú wọn wá fún àlùfáà, kí àlùfáà kọ́kọ́ mú èyí tó jẹ́ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ wá, kó sì já orí rẹ̀ níwájú ọrùn rẹ̀ láìjá a sọ́tọ̀ọ̀tọ̀. 9 Kó wọ́n lára ẹ̀jẹ̀ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ náà sí ẹ̀gbẹ́ pẹpẹ, àmọ́ kó ro ẹ̀jẹ̀ tó kù sí ìsàlẹ̀ pẹpẹ.+ Ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ ni. 10 Kó fi ìkejì rú ẹbọ sísun bí wọ́n ṣe máa ń ṣe é;+ kí àlùfáà sì ṣe ètùtù fún un torí ẹ̀ṣẹ̀ tó dá, yóò sì rí ìdáríjì.+
11 “‘Tí agbára rẹ̀ ò bá wá ká ẹyẹ oriri méjì tàbí ọmọ ẹyẹlé méjì, kó mú ìyẹ̀fun tó kúnná tó jẹ́ ìdá mẹ́wàá òṣùwọ̀n eéfà*+ wá láti fi rú ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ torí ẹ̀ṣẹ̀ tó dá. Kó má da òróró sí i, kó má sì fi oje igi tùràrí sí i, torí ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ ni. 12 Kó gbé e wá fún àlùfáà, kí àlùfáà sì bu ẹ̀kúnwọ́ ìyẹ̀fun náà, kó fi ṣe ọrẹ ìṣàpẹẹrẹ,* kó sì mú kó rú èéfín lórí pẹpẹ lórí àwọn ọrẹ àfinásun sí Jèhófà. Ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ ni. 13 Kí àlùfáà ṣe ètùtù fún un torí ẹ̀ṣẹ̀ tó dá, èyí tó wù kó jẹ́ nínú àwọn ẹ̀ṣẹ̀ yìí, yóò sì rí ìdáríjì.+ Èyí tó ṣẹ́ kù nínú ọrẹ náà yóò di ti àlùfáà,+ bíi ti ọrẹ ọkà.’”+
14 Jèhófà ń bá ọ̀rọ̀ tó ń sọ fún Mósè lọ pé: 15 “Tí ẹnì* kan bá hùwà àìṣòótọ́, ní ti pé ó ṣèèṣì ṣẹ̀ sí àwọn ohun mímọ́ Jèhófà,+ kó mú àgbò tí ara rẹ̀ dá ṣáṣá wá fún Jèhófà látinú agbo ẹran, kó fi rú ẹbọ ẹ̀bi;+ ṣékélì ibi mímọ́*+ ni kí wọ́n fi díwọ̀n iye ṣékélì* fàdákà rẹ̀. 16 Kó san nǹkan kan dípò ẹ̀ṣẹ̀ tó ṣẹ̀ sí ibi mímọ́, kó sì fi ìdá márùn-ún rẹ̀ kún un.+ Kó fún àlùfáà, kí àlùfáà lè fi àgbò ẹbọ ẹ̀bi ṣe ètùtù+ fún un, yóò sì rí ìdáríjì.+
17 “Tí ẹnì* kan bá ṣe èyíkéyìí nínú àwọn ohun tí Jèhófà pa láṣẹ pé kí ẹ má ṣe, tó sì tipa bẹ́ẹ̀ ṣẹ̀, bí kò bá tiẹ̀ mọ̀, yóò jìyà ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ torí ó ṣì jẹ̀bi.+ 18 Kó mú àgbò tí ara rẹ̀ dá ṣáṣá wá fún àlùfáà látinú agbo ẹran, láti fi rú ẹbọ ẹ̀bi,+ kí àgbò náà tó iye tí wọ́n dá lé e. Àlùfáà yóò wá ṣe ètùtù fún un torí àṣìṣe tó ṣe láìmọ̀ọ́mọ̀, yóò sì rí ìdáríjì. 19 Ẹbọ ẹ̀bi ni. Ó dájú pé ó ti jẹ̀bi torí ó ṣẹ Jèhófà.”
6 Jèhófà wá sọ fún Mósè pé: 2 “Tí ẹnì* kan bá ṣẹ̀, tó hùwà àìṣòótọ́ sí Jèhófà+ torí pé ó tan ọmọnìkejì rẹ̀ jẹ nípa ohun kan tó fi sí ìkáwọ́ rẹ̀ tàbí ohun kan tó fi pa mọ́ sọ́wọ́ rẹ̀+ tàbí tó ja ọmọnìkejì rẹ̀ lólè tàbí tó lù ú ní jìbìtì, 3 tàbí tó rí ohun tó sọ nù, tó sì sẹ́ pé òun ò rí i, tó wá búra èké lórí èyíkéyìí nínú ẹ̀ṣẹ̀ tó dá,+ ohun tó máa ṣe nìyí: 4 Tó bá ti ṣẹ̀, tó sì jẹ̀bi, kó dá ohun tó jí pa dà àti ohun tó fipá gbà, ohun tó fi jìbìtì gbà, ohun tí wọ́n fi sí ìkáwọ́ rẹ̀ tàbí ohun tó sọ nù tí ó rí, 5 tàbí ohunkóhun tó búra èké lé lórí, kó sì san gbogbo rẹ̀ pa dà,+ kó tún fi ìdá márùn-ún rẹ̀ kún un. Kó fún ẹni tó ni ín lọ́jọ́ tí wọ́n bá fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé ó jẹ̀bi. 6 Kó sì mú àgbò tí ara rẹ̀ dá ṣáṣá wá fún àlùfáà láti fi rú ẹbọ ẹ̀bi fún Jèhófà, kí àgbò náà tó iye tí wọ́n dá lé e, láti fi rú ẹbọ ẹ̀bi.+ 7 Kí àlùfáà ṣe ètùtù fún un níwájú Jèhófà, yóò sì rí ìdáríjì fún ohunkóhun tó ṣe tó mú kó jẹ̀bi.”+
8 Jèhófà ń bá ọ̀rọ̀ tó ń sọ fún Mósè lọ pé: 9 “Pàṣẹ fún Áárónì àti àwọn ọmọ rẹ̀ pé, ‘Òfin ẹbọ sísun+ nìyí: Kí ẹbọ sísun wà nínú ààrò lórí pẹpẹ ní gbogbo òru mọ́jú, kí iná sì máa jó lórí pẹpẹ náà. 10 Kí àlùfáà wọ ẹ̀wù oyè rẹ̀ tí wọ́n fi aṣọ ọ̀gbọ̀*+ ṣe, kó sì wọ ṣòkòtò péńpé*+ láti bo ara rẹ̀. Kó wá kó eérú*+ ẹbọ sísun tí wọ́n ti fi iná jó lórí pẹpẹ kúrò, kó sì kó o sẹ́gbẹ̀ẹ́ pẹpẹ. 11 Lẹ́yìn náà, kó bọ́ aṣọ rẹ̀,+ kó wọ aṣọ míì, kó sì kó eérú náà lọ síbì kan tó mọ́ lẹ́yìn ibùdó.+ 12 Kí iná máa jó lórí pẹpẹ. Kò gbọ́dọ̀ kú. Kí àlùfáà máa dáná igi + lórí rẹ̀ láràárọ̀, kó to ẹbọ sísun sórí rẹ̀, kó sì mú kí ọ̀rá ẹbọ ìrẹ́pọ̀ rú èéfín lórí rẹ̀.+ 13 Iná gbọ́dọ̀ máa jó lórí pẹpẹ náà nígbà gbogbo. Kò gbọ́dọ̀ kú.
14 “‘Òfin ọrẹ ọkà+ nìyí: Kí ẹ̀yin ọmọ Áárónì mú un wá síwájú Jèhófà, ní iwájú pẹpẹ. 15 Kí ọ̀kan lára wọn bu ẹ̀kúnwọ́ ìyẹ̀fun tó kúnná nínú ọrẹ ọkà àti díẹ̀ lára òróró rẹ̀ àti gbogbo oje igi tùràrí tó wà lórí ọrẹ ọkà, kó sì mú kó rú èéfín lórí pẹpẹ láti mú òórùn dídùn* jáde sí Jèhófà, kó fi ṣe ọrẹ ìṣàpẹẹrẹ.*+ 16 Kí Áárónì àti àwọn ọmọ rẹ̀ jẹ ohun tó bá ṣẹ́ kù lára rẹ̀.+ Kí wọ́n fi ṣe búrẹ́dì aláìwú, kí wọ́n jẹ ẹ́ ní ibi mímọ́. Kí wọ́n jẹ ẹ́ ní àgbàlá àgọ́ ìpàdé.+ 17 Wọn ò gbọ́dọ̀ fi ohunkóhun tó ní ìwúkàrà+ sí i. Mo ti fi ṣe ìpín tiwọn látinú àwọn ọrẹ àfinásun+ mi. Ohun mímọ́ jù lọ+ ni, bí ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ àti ẹbọ ẹ̀bi. 18 Gbogbo ọkùnrin nínú àwọn ọmọ Áárónì ni yóò jẹ+ ẹ́. Yóò jẹ́ ìpín wọn títí lọ látinú àwọn ọrẹ àfinásun+ sí Jèhófà, jálẹ̀ àwọn ìran wọn. Gbogbo ohun tó bá fara kàn wọ́n* yóò di mímọ́.’”
19 Jèhófà tún sọ fún Mósè pé: 20 “Èyí ni ọrẹ tí Áárónì àti àwọn ọmọ rẹ̀ yóò mú wá fún Jèhófà ní ọjọ́ tí ẹ bá fòróró yàn wọ́n:+ ìyẹ̀fun tó kúnná tó jẹ́ ìdá mẹ́wàá òṣùwọ̀n eéfà,*+ kí wọ́n máa fi ṣe ọrẹ ọkà+ nígbà gbogbo, ààbọ̀ rẹ̀ ní àárọ̀, ààbọ̀ rẹ̀ ní alẹ́. 21 Kí o fi òróró yan án lórí agbada.+ Kí o pò ó mọ́ òróró dáadáa, yan ọrẹ ọkà náà, kí o sì mú un wá ní kéékèèké fún Jèhófà bí ọrẹ tó ní òórùn dídùn.* 22 Àlùfáà tí ẹ fòróró yàn dípò rẹ̀ látinú àwọn ọmọ rẹ̀+ ni kó ṣe é. Ìlànà tó máa wà títí lọ ni: Kó jẹ́ odindi ọrẹ tó máa mú kó rú èéfín sí Jèhófà. 23 Kí gbogbo ọrẹ ọkà àlùfáà jẹ́ odindi ọrẹ. Wọn ò gbọ́dọ̀ jẹ ẹ́.”
24 Jèhófà tún sọ fún Mósè pé: 25 “Sọ fún Áárónì àti àwọn ọmọ rẹ̀ pé, ‘Òfin ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀+ nìyí: Ibi tí wọ́n ti ń pa ẹran ẹbọ sísun+ ni kí wọ́n ti pa ẹran ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ níwájú Jèhófà. Ohun mímọ́ jù lọ ni. 26 Àlùfáà tó fi rú ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ ló máa jẹ ẹ́.+ Ibi mímọ́ ni kó ti jẹ ẹ́, nínú àgbàlá àgọ́ ìpàdé.+
27 “‘Gbogbo ohun tó bá fara kan ẹran rẹ̀ yóò di mímọ́, tí ẹnikẹ́ni bá sì wọ́n lára ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ sí aṣọ rẹ̀, kí o fọ aṣọ tí ẹni náà wọ́n ẹ̀jẹ̀ sí ní ibi mímọ́. 28 Kí wọ́n fọ́ ìkòkò amọ̀ tí wọ́n fi sè é túútúú. Àmọ́ tó bá jẹ́ ìkòkò bàbà ni wọ́n fi sè é, kí wọ́n ha á, kí wọ́n sì fi omi fọ̀ ọ́.
29 “‘Gbogbo ọkùnrin tó jẹ́ àlùfáà ni kó jẹ ẹ́.+ Ohun mímọ́ jù lọ+ ni. 30 Àmọ́, ẹ ò gbọ́dọ̀ jẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ tí wọ́n ti mú lára ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ wá sínú àgọ́ ìpàdé láti ṣe ètùtù ní ibi mímọ́.+ Ṣe ni kí ẹ fi iná sun ún.
7 “‘Òfin ẹbọ ẹ̀bi+ nìyí: Ohun mímọ́ jù lọ ni. 2 Ibi tí wọ́n ti ń pa ẹran ẹbọ sísun ni kí wọ́n ti pa ẹran ẹbọ ẹ̀bi, kí wọ́n sì wọ́n ẹ̀jẹ̀ rẹ̀+ sí gbogbo ẹ̀gbẹ́ pẹpẹ.+ 3 Kó mú gbogbo ọ̀rá rẹ̀+ wá, pẹ̀lú ìrù ọlọ́ràá, ọ̀rá tó bo ìfun 4 àti kíndìnrín méjèèjì pẹ̀lú ọ̀rá wọn tó wà nítòsí abẹ́nú. Kó tún yọ àmọ́ tó wà lára ẹ̀dọ̀ pẹ̀lú àwọn kíndìnrín náà.+ 5 Kí àlùfáà mú kí wọ́n rú èéfín lórí pẹpẹ, kó fi ṣe ọrẹ àfinásun sí Jèhófà.+ Ẹbọ ẹ̀bi ni. 6 Kí gbogbo ọkùnrin tó jẹ́ àlùfáà jẹ ẹ́,+ ibi mímọ́ ni kí wọ́n sì ti jẹ ẹ́. Ohun mímọ́ jù lọ ni.+ 7 Òfin ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ náà kan ẹbọ ẹ̀bi; àlùfáà tó fi ṣe ètùtù ló ni ín.+
8 “‘Tí àlùfáà bá mú ẹbọ sísun tó jẹ́ ti ẹnì kan wá, awọ+ ẹran ẹbọ sísun tó mú wá fún àlùfáà yóò di tirẹ̀.
9 “‘Gbogbo ọrẹ ọkà tí wọ́n bá yan nínú ààrò tàbí tí wọ́n sè nínú páànù tàbí nínú agbada+ jẹ́ ti àlùfáà tó mú un wá. Yóò di tirẹ̀.+ 10 Àmọ́ gbogbo ọrẹ ọkà tí wọ́n pò mọ́ òróró+ tàbí tó gbẹ+ yóò jẹ́ ti gbogbo àwọn ọmọ Áárónì; ìpín kálukú máa dọ́gba.
11 “‘Òfin ẹbọ ìrẹ́pọ̀+ tí ẹnì kan bá mú wá fún Jèhófà nìyí: 12 Tó bá mú un wá láti fi ṣe ìdúpẹ́,+ kó mú ẹbọ ìdúpẹ́ náà wá pẹ̀lú búrẹ́dì aláìwú tí wọ́n pò mọ́ òróró, tó sì rí bí òrùka, búrẹ́dì aláìwú pẹlẹbẹ tí wọ́n pò mọ́ òróró àti búrẹ́dì tó rí bí òrùka tí wọ́n fi ìyẹ̀fun tó kúnná ṣe, tí wọ́n pò dáadáa tí wọ́n sì pò mọ́ òróró. 13 Kó mú ọrẹ rẹ̀ wá pẹ̀lú búrẹ́dì tí wọ́n fi ìwúkàrà sí tó rí bí òrùka, kó sì mú ẹbọ ìdúpẹ́ ti ẹbọ ìrẹ́pọ̀ rẹ̀ wá. 14 Kó mú ọ̀kan lára ọrẹ kọ̀ọ̀kan wá nínú rẹ̀ láti fi ṣe ìpín mímọ́ fún Jèhófà; yóò di ti àlùfáà tó wọ́n ẹ̀jẹ̀ ẹbọ ìrẹ́pọ̀.+ 15 Ọjọ́ tó bá mú ẹbọ ìdúpẹ́ ti ẹbọ ìrẹ́pọ̀ rẹ̀ wá ni kó jẹ ẹran rẹ̀. Kò gbọ́dọ̀ ṣẹ́ ìkankan nínú rẹ̀ kù di àárọ̀.+
16 “‘Tí ohun tó bá fi rúbọ bá jẹ́ ti ẹ̀jẹ́+ tàbí ọrẹ àtinúwá,+ ọjọ́ tó bá mú ọrẹ rẹ̀ wá ni kó jẹ ẹ́, kó sì jẹ ohun tó bá ṣẹ́ kù lára rẹ̀ ní ọjọ́ kejì. 17 Àmọ́ kó fi iná sun+ ohunkóhun tó bá ṣẹ́ kù di ọjọ́ kẹta lára ẹran tó fi rúbọ. 18 Tí wọ́n bá jẹ èyíkéyìí lára ẹran ẹbọ ìrẹ́pọ̀ rẹ̀ ní ọjọ́ kẹta, ẹni tó mú un wá kò ní rí ìtẹ́wọ́gbà. Kò ní rí ojú rere; ohun tí kò tọ́ ni, ẹni* tó bá sì jẹ lára rẹ̀ yóò jìyà ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀.+ 19 Ẹ ò gbọ́dọ̀ jẹ ẹran tó bá fara kan ohun àìmọ́ èyíkéyìí. Ṣe ni kí ẹ fi iná sun ún. Gbogbo ẹni tó bá mọ́ lè jẹ ẹran tó mọ́.
20 “‘Àmọ́ tí ẹnikẹ́ni* tó jẹ́ aláìmọ́ bá jẹ ẹran ẹbọ ìrẹ́pọ̀, tó jẹ́ ti Jèhófà, kí ẹ pa ẹni* náà, kí ẹ lè mú un kúrò láàárín àwọn èèyàn rẹ̀.+ 21 Tí ẹnì* kan bá fara kan ohunkóhun tó jẹ́ aláìmọ́, yálà ohun àìmọ́ ti èèyàn+ tàbí ẹranko aláìmọ́+ tàbí ohunkóhun tó jẹ́ aláìmọ́ tó sì ń ríni lára,+ tí ẹni náà sì jẹ lára ẹran ẹbọ ìrẹ́pọ̀ náà, tó jẹ́ ti Jèhófà, kí ẹ pa ẹni* náà, kí ẹ lè mú un kúrò láàárín àwọn èèyàn rẹ̀.’”
22 Jèhófà ń bá ọ̀rọ̀ tó ń sọ fún Mósè lọ pé: 23 “Sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé, ‘Ẹ ò gbọ́dọ̀ jẹ ọ̀rá+ èyíkéyìí láti ara akọ màlúù tàbí ọmọ àgbò tàbí ewúrẹ́. 24 Ẹ lè fi ọ̀rá òkú ẹran àti ọ̀rá ẹran tí ẹranko míì pa ṣe nǹkan míì, àmọ́ ẹ ò gbọ́dọ̀ jẹ ẹ́.+ 25 Tí ẹnikẹ́ni bá jẹ ọ̀rá ẹran tó mú wá láti fi ṣe ọrẹ àfinásun sí Jèhófà, kí ẹ pa onítọ̀hún kí ẹ lè mú un kúrò láàárín àwọn èèyàn rẹ̀.
26 “‘Ẹ ò gbọ́dọ̀ jẹ ẹ̀jẹ̀ èyíkéyìí+ ní gbogbo ibi tí ẹ̀ ń gbé, ì báà jẹ́ ti ẹyẹ tàbí ti ẹranko. 27 Kí ẹ pa ẹnikẹ́ni* tó bá jẹ ẹ̀jẹ̀ èyíkéyìí kí ẹ lè mú un kúrò+ láàárín àwọn èèyàn rẹ̀.’”
28 Jèhófà wá sọ fún Mósè pé: 29 “Sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé, ‘Kí ẹnikẹ́ni tó bá fẹ́ mú ẹbọ ìrẹ́pọ̀ wá fún Jèhófà mú ọrẹ wá fún Jèhófà látinú ẹbọ ìrẹ́pọ̀ rẹ̀.+ 30 Ọwọ́ ara rẹ̀ ni kó fi mú ọ̀rá+ pẹ̀lú igẹ̀ wá láti fi ṣe ọrẹ àfinásun sí Jèhófà, kó sì fì í síwá-sẹ́yìn bí ọrẹ fífì+ níwájú Jèhófà. 31 Kí àlùfáà mú kí ọ̀rá náà rú èéfín lórí pẹpẹ,+ àmọ́ igẹ̀ náà jẹ́ ti Áárónì àti àwọn ọmọ rẹ̀.+
32 “‘Kí ẹ fún àlùfáà ní ẹsẹ̀ ọ̀tún, kó jẹ́ ìpín mímọ́ tirẹ̀ látinú àwọn ẹbọ ìrẹ́pọ̀+ yín. 33 Kí ẹsẹ̀ ọ̀tún jẹ́ ìpín+ ọmọ Áárónì tó bá mú ẹ̀jẹ̀ ẹbọ ìrẹ́pọ̀ àti ọ̀rá wá. 34 Torí mo mú igẹ̀ ọrẹ fífì àti ẹsẹ̀ ìpín mímọ́ náà látinú àwọn ẹbọ ìrẹ́pọ̀ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, mo sì fún àlùfáà Áárónì àti àwọn ọmọ rẹ̀, kó jẹ́ ìlànà tó máa wà fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì+ títí lọ.
35 “‘Ìpín tí wọ́n yà sọ́tọ̀ fún àwọn àlùfáà nìyí, fún Áárónì àti àwọn ọmọ rẹ̀, látinú àwọn ọrẹ àfinásun sí Jèhófà, ní ọjọ́ tó mú wọn wá síwájú Jèhófà láti ṣe àlùfáà rẹ̀.+ 36 Jèhófà pàṣẹ pé kí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì fún wọn ní ìpín yìí lọ́jọ́ tó fòróró yàn wọ́n.+ Àṣẹ tí wọ́n á máa pa mọ́ títí láé jálẹ̀ àwọn ìran wọn ni.’”
37 Èyí ni òfin nípa ẹbọ sísun,+ ọrẹ ọkà,+ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀,+ ẹbọ ẹ̀bi,+ ẹbọ ìyannisípò+ àti ẹbọ ìrẹ́pọ̀,+ 38 bí Jèhófà ṣe pa á láṣẹ fún Mósè lórí Òkè Sínáì+ lọ́jọ́ tó pàṣẹ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé kí wọ́n mú ọrẹ wọn wá fún Jèhófà ní aginjù Sínáì.+
8 Jèhófà wá sọ fún Mósè pé: 2 “Mú Áárónì àti àwọn ọmọ rẹ̀+ pẹ̀lú àwọn aṣọ,+ òróró àfiyanni,+ akọ màlúù ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, àgbò méjì àti apẹ̀rẹ̀ búrẹ́dì aláìwú,+ 3 kí o sì mú kí gbogbo àpéjọ náà kóra jọ sí ẹnu ọ̀nà àgọ́ ìpàdé.”
4 Mósè ṣe ohun tí Jèhófà pa láṣẹ fún un gẹ́lẹ́, àpéjọ náà sì kóra jọ sí ẹnu ọ̀nà àgọ́ ìpàdé. 5 Mósè sọ fún àpéjọ àwọn èèyàn náà pé: “Ohun tí Jèhófà pa láṣẹ pé ká ṣe nìyí.” 6 Mósè wá mú Áárónì àti àwọn ọmọ rẹ̀ sún mọ́ tòsí, ó sì fi omi wẹ̀ wọ́n.+ 7 Lẹ́yìn náà, ó wọ aṣọ+ fún un, ó de ọ̀já+ mọ́ ọn, ó wọ aṣọ àwọ̀lékè tí kò lápá+ fún un, ó wọ éfódì+ fún un, ó sì fi àmùrè éfódì tí wọ́n hun pọ̀*+ dè é mọ́ ọn pinpin. 8 Ó wá wọ aṣọ ìgbàyà+ fún un, ó sì fi Úrímù àti Túmímù+ sí aṣọ ìgbàyà náà. 9 Lẹ́yìn náà, ó wé láwàní+ sí i lórí, ó sì fi irin wúrà pẹlẹbẹ tó ń dán tó jẹ́ àmì mímọ́ ti ìyàsímímọ́*+ sí iwájú láwàní náà, bí Jèhófà ṣe pa á láṣẹ fún Mósè.
10 Mósè bá mú òróró àfiyanni, ó sì fòróró yan àgọ́ ìjọsìn àti gbogbo ohun tó wà nínú rẹ̀,+ ó sì yà wọ́n sí mímọ́. 11 Lẹ́yìn náà, ó wọ́n lára rẹ̀ sórí pẹpẹ lẹ́ẹ̀méje, ó sì fòróró yan pẹpẹ àti gbogbo ohun èlò rẹ̀ àti bàsíà àti ẹsẹ̀ rẹ̀ láti yà wọ́n sí mímọ́. 12 Níkẹyìn, ó dà lára òróró àfiyanni sórí Áárónì, ó sì fòróró yàn án láti sọ ọ́ di mímọ́.+
13 Mósè mú àwọn ọmọ Áárónì sún mọ́ tòsí, ó wọ aṣọ fún wọn, ó so ọ̀já mọ́ wọn lára, ó sì wé* aṣọ sí wọn lórí,+ bí Jèhófà ṣe pa á láṣẹ fún un.
14 Lẹ́yìn náà, ó mú akọ màlúù ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ wá, Áárónì àti àwọn ọmọ rẹ̀ sì gbé ọwọ́ lé orí akọ màlúù ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀+ náà. 15 Mósè pa á, ó fi ìka rẹ̀ mú ẹ̀jẹ̀ ẹran náà,+ ó fi sára àwọn ìwo tó wà ní gbogbo ẹ̀gbẹ́ pẹpẹ, ó sì wẹ ẹ̀ṣẹ̀ kúrò lára pẹpẹ náà, àmọ́ ó da ẹ̀jẹ̀ tó kù sí ìsàlẹ̀ pẹpẹ, kó lè yà á sí mímọ́ láti ṣe ètùtù lórí rẹ̀. 16 Lẹ́yìn náà, ó mú gbogbo ọ̀rá tó wà lára ìfun, àmọ́ tó wà lára ẹ̀dọ̀, kíndìnrín méjèèjì àti ọ̀rá wọn, Mósè sì mú kí wọ́n rú èéfín lórí pẹpẹ.+ 17 Ó wá fi iná sun ohun tó ṣẹ́ kù lára akọ màlúù náà, awọ rẹ̀, ẹran rẹ̀ àti ìgbẹ́ rẹ̀ ní ẹ̀yìn ibùdó+ bí Jèhófà ṣe pa á láṣẹ fún un.
18 Ó mú àgbò tó fẹ́ fi rú ẹbọ sísun náà wá sí tòsí, Áárónì àti àwọn ọmọ rẹ̀ sì gbé ọwọ́ lé orí àgbò náà.+ 19 Lẹ́yìn náà, Mósè pa á, ó sì wọ́n ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ sí gbogbo ẹ̀gbẹ́ pẹpẹ. 20 Ó gé àgbò náà sí wẹ́wẹ́, Mósè sì mú kí orí àgbò náà, àwọn ègé rẹ̀ àti ọ̀rá rẹ̀ líle* rú èéfín. 21 Ó fi omi fọ ìfun àti ẹsẹ̀ rẹ̀, Mósè sì mú kí odindi àgbò náà rú èéfín lórí pẹpẹ. Ẹbọ sísun tó ní òórùn dídùn* ni. Ọrẹ àfinásun sí Jèhófà ló jẹ́, bí Jèhófà ṣe pa á láṣẹ fún Mósè.
22 Lẹ́yìn náà, ó mú àgbò kejì wá, àgbò àfiyanni,+ Áárónì àti àwọn ọmọ rẹ̀ sì gbé ọwọ́ lé orí àgbò náà.+ 23 Mósè pa á, ó sì mú lára ẹ̀jẹ̀ rẹ̀, ó fi sí ìsàlẹ̀ etí ọ̀tún Áárónì àti àtàǹpàkò ọwọ́ rẹ̀ ọ̀tún àti àtàǹpàkò ẹsẹ̀ rẹ̀ ọ̀tún. 24 Lẹ́yìn náà, Mósè mú àwọn ọmọ Áárónì wá síwájú, ó sì fi lára ẹ̀jẹ̀ náà sí ìsàlẹ̀ etí wọn ọ̀tún àti àtàǹpàkò ọwọ́ wọn ọ̀tún àti àtàǹpàkò ẹsẹ̀ wọn ọ̀tún; àmọ́ Mósè wọ́n ẹ̀jẹ̀ tó kù sí gbogbo ẹ̀gbẹ́ pẹpẹ náà.+
25 Ó wá mú ọ̀rá rẹ̀, ìrù ọlọ́ràá, gbogbo ọ̀rá tó wà lára ìfun, àmọ́ tó wà lára ẹ̀dọ̀, kíndìnrín méjèèjì àti ọ̀rá wọn, pẹ̀lú ẹsẹ̀ ọ̀tún.+ 26 Ó mú búrẹ́dì aláìwú kan tó rí bí òrùka,+ búrẹ́dì kan tí wọ́n fi òróró sí tó rí bí òrùka+ àti búrẹ́dì pẹlẹbẹ kan látinú apẹ̀rẹ̀ búrẹ́dì aláìwú tó wà níwájú Jèhófà. Ó sì kó wọn sórí àwọn ọ̀rá náà àti ẹsẹ̀ ọ̀tún. 27 Lẹ́yìn náà, ó kó gbogbo rẹ̀ sórí àtẹ́lẹwọ́ Áárónì àti àwọn ọmọ rẹ̀, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í fì ọrẹ náà síwá-sẹ́yìn bí ọrẹ fífì níwájú Jèhófà. 28 Lẹ́yìn náà, Mósè gbà á lọ́wọ́ wọn, ó sì mú kí wọ́n rú èéfín lórí pẹpẹ lórí ẹbọ sísun. Wọ́n jẹ́ ẹbọ ìyannisípò tó ní òórùn dídùn.* Ọrẹ àfinásun sí Jèhófà ni.
29 Mósè tún mú igẹ̀, ó sì fì í síwá-sẹ́yìn bí ọrẹ fífì níwájú Jèhófà.+ Ó di ìpín Mósè látinú àgbò àfiyanni, bí Jèhófà ṣe pa á láṣẹ fún un.+
30 Mósè mú lára òróró àfiyanni,+ ó sì mú lára ẹ̀jẹ̀ tó wà lórí pẹpẹ, ó wọ́n ọn sára Áárónì àti aṣọ rẹ̀ àti sára àwọn ọmọ rẹ̀ àti aṣọ àwọn ọmọ rẹ̀ tó wà pẹ̀lú rẹ̀. Bó ṣe sọ Áárónì àti aṣọ rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ọmọ rẹ̀+ àti aṣọ wọn+ di mímọ́ nìyẹn.
31 Lẹ́yìn náà, Mósè sọ fún Áárónì àti àwọn ọmọ rẹ̀ pé: “Ẹ se+ ẹran náà ní ẹnu ọ̀nà àgọ́ ìpàdé, ibẹ̀ sì ni kí ẹ ti jẹ ẹ́ pẹ̀lú búrẹ́dì tó wà nínú apẹ̀rẹ̀ àfiyanni, bí àṣẹ tí mo gbà tó sọ pé, ‘Kí Áárónì àti àwọn ọmọ rẹ̀ jẹ ẹ́.’+ 32 Kí ẹ fi iná sun ẹran àti búrẹ́dì tó bá ṣẹ́ kù.+ 33 Ẹ ò gbọ́dọ̀ jáde ní ẹnu ọ̀nà àgọ́ ìpàdé fún ọjọ́ méje, títí ọjọ́ tí wọ́n á fa iṣẹ́ lé yín lọ́wọ́ yóò fi pé, torí ọjọ́ méje ló máa gbà láti sọ yín di àlùfáà.*+ 34 Jèhófà pàṣẹ pé ká ṣe ohun tí a ṣe lónìí láti ṣe ètùtù fún yín.+ 35 Kí ẹ wà ní ẹnu ọ̀nà àgọ́ ìpàdé tọ̀sántòru fún ọjọ́ méje,+ kí ẹ sì ṣe ohun tí Jèhófà ní kí ẹ ṣe,+ kí ẹ má bàa kú; torí àṣẹ tí mo gbà ni.”
36 Áárónì àti àwọn ọmọ rẹ̀ sì ṣe gbogbo ohun tí Jèhófà pa láṣẹ nípasẹ̀ Mósè.
9 Ní ọjọ́ kẹjọ,+ Mósè pe Áárónì àti àwọn ọmọ rẹ̀ àti àwọn àgbààgbà Ísírẹ́lì. 2 Ó sọ fún Áárónì pé: “Mú ọmọ màlúù kan fún ara rẹ láti fi rú ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀+ àti àgbò kan láti fi rú ẹbọ sísun, kí ara wọn dá ṣáṣá, kí o sì mú wọn wá síwájú Jèhófà. 3 Àmọ́ kí o sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé, ‘Ẹ mú akọ ewúrẹ́ kan láti fi rú ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ àti ọmọ màlúù kan àti ọmọ àgbò kan, kí ọ̀kọ̀ọ̀kan jẹ́ ọlọ́dún kan tí ara rẹ̀ dá ṣáṣá, kí ẹ fi rú ẹbọ sísun, 4 kí ẹ sì mú akọ màlúù kan àti àgbò kan láti fi rú ẹbọ ìrẹ́pọ̀,+ kí ẹ fi wọ́n rúbọ níwájú Jèhófà, pẹ̀lú ọrẹ ọkà+ tí ẹ pò mọ́ òróró, torí Jèhófà yóò fara hàn+ yín lónìí.’”
5 Wọ́n mú ohun tí Mósè pa láṣẹ wá síwájú àgọ́ ìpàdé. Ni gbogbo àpéjọ náà bá sún mọ́ iwájú, wọ́n sì dúró níwájú Jèhófà. 6 Mósè sì sọ pé: “Ohun tí Jèhófà pàṣẹ pé kí ẹ ṣe nìyí, kí Jèhófà lè fi ògo rẹ̀ hàn yín.”+ 7 Mósè wá sọ fún Áárónì pé: “Sún mọ́ pẹpẹ, kí o rú ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀+ rẹ àti ẹbọ sísun, kí o sì ṣe ètùtù fún ara rẹ+ àti ilé rẹ; mú ọrẹ àwọn èèyàn náà wá,+ kí o sì ṣe ètùtù fún wọn,+ bí Jèhófà ṣe pa á láṣẹ.”
8 Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, Áárónì sún mọ́ pẹpẹ, ó sì pa ọmọ màlúù ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ tó jẹ́ tirẹ̀.+ 9 Lẹ́yìn náà, àwọn ọmọ Áárónì gbé ẹ̀jẹ̀+ ẹran náà wá fún un, ó ki ìka rẹ̀ bọ ẹ̀jẹ̀ náà, ó sì fi sára àwọn ìwo pẹpẹ, ó wá da ẹ̀jẹ̀ tó kù sí ìsàlẹ̀ pẹpẹ.+ 10 Ó mú kí ọ̀rá àti àwọn kíndìnrín àti àmọ́ tó wà lára ẹ̀dọ̀ látinú ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ náà rú èéfín lórí pẹpẹ, bí Jèhófà ṣe pa á láṣẹ fún Mósè.+ 11 Ó sì fi iná sun ẹran náà àti awọ rẹ̀ lẹ́yìn ibùdó.+
12 Lẹ́yìn náà, ó pa ẹran ẹbọ sísun náà, àwọn ọmọ Áárónì gbé ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ fún un, ó sì wọ́n ọn sí gbogbo ẹ̀gbẹ́ pẹpẹ náà.+ 13 Wọ́n kó àwọn ègé ẹran ẹbọ sísun náà àti orí rẹ̀ fún un, ó sì mú kó rú èéfín lórí pẹpẹ. 14 Ó tún fọ ìfun àti ẹsẹ̀ rẹ̀, ó sì mú kó rú èéfín lórí ẹbọ sísun tó wà lórí pẹpẹ.
15 Lẹ́yìn náà, ó mú ọrẹ àwọn èèyàn náà wá, ó mú ewúrẹ́ tó fẹ́ fi rú ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ fún àwọn èèyàn náà, ó sì pa á, ó sì fi rú ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ bíi ti àkọ́kọ́. 16 Ó mú ẹbọ sísun náà wá, ó sì ṣe é bí wọ́n ṣe ń ṣe é.+
17 Lẹ́yìn náà, ó mú ọrẹ ọkà+ wá, ó bu ẹ̀kúnwọ́ rẹ̀, ó sì mú kó rú èéfín lórí pẹpẹ, yàtọ̀ sí ẹbọ sísun tó sun ní àárọ̀.+
18 Lẹ́yìn ìyẹn, ó pa akọ màlúù àti àgbò ẹbọ ìrẹ́pọ̀ tó jẹ́ ti àwọn èèyàn náà. Àwọn ọmọ Áárónì wá gbé ẹ̀jẹ̀ náà fún un, ó sì wọ́n ọn yí ká gbogbo ẹ̀gbẹ́ pẹpẹ.+ 19 Ní ti àwọn ọ̀rá akọ màlúù náà,+ ìrù àgbò náà tó lọ́ràá, ọ̀rá tó bo àwọn ohun tó wà nínú ẹran náà, àwọn kíndìnrín àti àmọ́ tó wà lára ẹ̀dọ̀,+ 20 wọ́n kó gbogbo àwọn ọ̀rá náà sórí àwọn igẹ̀, lẹ́yìn náà, ó mú kí àwọn ọ̀rá náà rú èéfín lórí pẹpẹ.+ 21 Àmọ́ Áárónì fi àwọn igẹ̀ àti ẹsẹ̀ ọ̀tún síwá-sẹ́yìn bí ọrẹ fífì níwájú Jèhófà, bí Mósè ṣe pa á láṣẹ.+
22 Áárónì wá kọjú sí àwọn èèyàn náà, ó sì gbé ọwọ́ rẹ̀ sókè, ó súre fún wọn,+ ó sì sọ̀ kalẹ̀ kúrò níbi tó ti ń fi ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, ẹbọ sísun àti ẹbọ ìrẹ́pọ̀ rúbọ. 23 Níkẹyìn, Mósè àti Áárónì lọ sínú àgọ́ ìpàdé, wọ́n jáde wá, wọ́n sì súre fún àwọn èèyàn náà.+
Jèhófà wá fi ògo rẹ̀ han gbogbo àwọn èèyàn náà,+ 24 iná sì bọ́ láti ọ̀dọ̀ Jèhófà,+ ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í jó ẹbọ sísun àti àwọn ọ̀rá tó wà lórí pẹpẹ. Nígbà tí gbogbo àwọn èèyàn náà rí i, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í kígbe, wọ́n sì dojú bolẹ̀.+
10 Lẹ́yìn náà, àwọn ọmọ Áárónì, Nádábù àti Ábíhù,+ mú ìkóná wọn, kálukú fi iná sínú rẹ̀, wọ́n sì fi tùràrí+ sórí rẹ̀. Wọ́n wá bẹ̀rẹ̀ sí í rú ẹbọ tí kò yẹ+ níwájú Jèhófà, ohun tí kò pa láṣẹ fún wọn. 2 Ni iná bá bọ́ látọ̀dọ̀ Jèhófà, ó sì jó wọn run,+ wọ́n sì kú níwájú Jèhófà.+ 3 Mósè wá sọ fún Áárónì pé: “Ohun tí Jèhófà sọ nìyí, ‘Àwọn tó sún mọ́ mi+ yóò mọ̀ pé mímọ́ ni mí, wọ́n á sì yìn mí lógo níṣojú gbogbo èèyàn.’” Áárónì sì dákẹ́ jẹ́ẹ́.
4 Mósè bá pe Míṣáẹ́lì àti Élísáfánì, àwọn ọmọ Úsíélì,+ arákùnrin bàbá Áárónì, ó sì sọ fún wọn pé: “Ẹ wá gbé àwọn arákùnrin yín kúrò níwájú ibi mímọ́ lọ síbì kan lẹ́yìn ibùdó.” 5 Torí náà, wọ́n wá, wọ́n sì gbé àwọn ọkùnrin náà lọ sí ibì kan lẹ́yìn ibùdó pẹ̀lú aṣọ ara wọn, bí Mósè ṣe sọ fún wọn.
6 Mósè wá sọ fún Áárónì àti àwọn ọmọ rẹ̀ yòókù, Élíásárì àti Ítámárì, pé: “Ẹ má fi irun orí yín sílẹ̀ láìtọ́jú, ẹ ò sì gbọ́dọ̀ ya aṣọ yín,+ kí ẹ má bàa kú, kí Ọlọ́run má bàa bínú sí gbogbo àpéjọ yìí. Àwọn arákùnrin yín ní gbogbo ilé Ísírẹ́lì máa sunkún torí àwọn tí Jèhófà fi iná pa. 7 Ẹ ò gbọ́dọ̀ jáde ní ẹnu ọ̀nà àgọ́ ìpàdé, àìjẹ́ bẹ́ẹ̀, ẹ máa kú, torí òróró àfiyanni Jèhófà wà lórí yín.”+ Torí náà, wọ́n ṣe ohun tí Mósè sọ.
8 Lẹ́yìn náà, Jèhófà sọ fún Áárónì pé: 9 “Ìwọ àti àwọn ọmọ rẹ ò gbọ́dọ̀ mu wáìnì tàbí àwọn ohun mímu míì tó ní ọtí nígbà tí ẹ bá wá sínú àgọ́ ìpàdé,+ kí ẹ má bàa kú. Àṣẹ tí ìran yín á máa pa mọ́ títí láé ni. 10 Èyí máa fi ìyàtọ̀ sáàárín ohun mímọ́ àti ohun tó di aláìmọ́ àti sáàárín ohun tí kò mọ́ àti ohun tó mọ́,+ 11 yóò sì tún kọ́ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní gbogbo ìlànà tí Jèhófà sọ fún wọn nípasẹ̀ Mósè.”+
12 Mósè wá sọ fún Áárónì àti àwọn ọmọ rẹ̀ yòókù, Élíásárì àti Ítámárì pé: “Ẹ kó ọrẹ ọkà tó ṣẹ́ kù látinú àwọn ọrẹ àfinásun sí Jèhófà, kí ẹ fi ṣe búrẹ́dì aláìwú, kí ẹ sì jẹ ẹ́ nítòsí pẹpẹ,+ torí pé ohun mímọ́ jù lọ ni.+ 13 Kí ẹ jẹ ẹ́ ní ibi mímọ́,+ torí ìpín tìrẹ àti ìpín àwọn ọmọ rẹ látinú àwọn ọrẹ àfinásun sí Jèhófà ni, torí pé àṣẹ tí mo gbà nìyí. 14 Kí ìwọ àti àwọn ọmọ rẹ lọ́kùnrin àti lóbìnrin+ tún jẹ igẹ̀ ọrẹ fífì àti ẹsẹ̀ ìpín mímọ́+ ní ibi tó mọ́, torí mo ti fi ṣe ìpín rẹ àti ti àwọn ọmọ rẹ látinú ẹbọ ìrẹ́pọ̀ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì. 15 Kí wọ́n mú ẹsẹ̀ ìpín mímọ́ wá pẹ̀lú igẹ̀ ọrẹ fífì àti àwọn ọrẹ ọ̀rá tí wọ́n fi iná sun, kí wọ́n lè fi ọrẹ fífì náà síwá-sẹ́yìn níwájú Jèhófà; yóò jẹ́ ìpín rẹ àti ti àwọn ọmọ+ rẹ títí lọ, bí Jèhófà ṣe pa á láṣẹ.”
16 Mósè fara balẹ̀ wá ewúrẹ́ tí wọ́n fi rú ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀+ náà, ó sì rí i pé wọ́n ti sun ún. Ni inú bá bí i sí Élíásárì àti Ítámárì, àwọn ọmọ Áárónì yòókù, ó sì sọ pé: 17 “Kí ló dé tí ẹ ò jẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ náà ní ibi mímọ́,+ ṣebí ohun mímọ́ jù lọ ni, ó sì ti fún yín, kí ẹ lè ru ẹ̀bi àpéjọ náà, kí ẹ sì ṣe ètùtù fún wọn níwájú Jèhófà? 18 Ẹ wò ó! Ẹ ò tíì gbé ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ wá sínú ibi mímọ́.+ Ó yẹ kí ẹ ti jẹ ẹ́ ní ibi mímọ́, bí àṣẹ tí mo gbà.” 19 Áárónì sọ fún Mósè pé: “Wò ó! Wọ́n mú ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ wọn àti ẹbọ sísun wọn wá síwájú Jèhófà+ lónìí, síbẹ̀ nǹkan wọ̀nyí ṣẹlẹ̀ sí mi. Ká ní mo jẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ lónìí ni, ṣé inú Jèhófà máa dùn?” 20 Nígbà tí Mósè gbọ́ ọ̀rọ̀ yẹn, ó tẹ́ ẹ lọ́rùn.
11 Jèhófà wá sọ fún Mósè àti Áárónì pé: 2 “Ẹ sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé, ‘Àwọn ohun alààyè tó wà ní ayé* tí ẹ lè jẹ+ nìyí: 3 Ẹ lè jẹ gbogbo ẹran tí pátákò rẹ̀ là, tí pátákò rẹ̀ ní àlàfo, tó sì ń jẹ àpọ̀jẹ.
4 “‘Àmọ́ ẹ ò gbọ́dọ̀ jẹ àwọn ẹran yìí tó ń jẹ àpọ̀jẹ tàbí àwọn tí pátákò wọn là: ràkúnmí máa ń jẹ àpọ̀jẹ, àmọ́ pátákò rẹ̀ kò là. Aláìmọ́ ló jẹ́ fún yín.+ 5 Bákan náà, gara orí àpáta + máa ń jẹ àpọ̀jẹ, àmọ́ pátákò rẹ̀ kò là. Aláìmọ́ ló jẹ́ fún yín. 6 Ehoro pẹ̀lú máa ń jẹ àpọ̀jẹ, àmọ́ pátákò rẹ̀ kò là. Aláìmọ́ ló jẹ́ fún yín. 7 Bákan náà ni ẹlẹ́dẹ̀,+ torí pátákò rẹ̀ là, ó sì ní àlàfo, àmọ́ kì í jẹ àpọ̀jẹ. Aláìmọ́ ló jẹ́ fún yín. 8 Ẹ ò gbọ́dọ̀ jẹ èyíkéyìí nínú ẹran wọn, ẹ ò sì gbọ́dọ̀ fara kan òkú wọn. Aláìmọ́ ni wọ́n jẹ́ fún yín.+
9 “‘Èyí tí ẹ lè jẹ nínú gbogbo ohun tó wà nínú omi nìyí: Ẹ lè jẹ+ ohunkóhun tó wà nínú omi tó ní lẹ́bẹ́ àti ìpẹ́, ì báà jẹ́ inú òkun tàbí inú odò ló wà. 10 Àmọ́ ohunkóhun tó wà nínú òkun àti odò tí kò ní lẹ́bẹ́ àti ìpẹ́, nínú gbogbo ẹ̀dá tó ń gbá yìn-ìn àti gbogbo ohun alààyè* míì tó wà nínú omi, ohun ìríra ló jẹ́ fún yín. 11 Àní ohun ìríra ni wọ́n gbọ́dọ̀ jẹ́ fún yín, ẹ ò gbọ́dọ̀ jẹ èyíkéyìí nínú ẹran wọn,+ kí ẹ sì ka òkú wọn sí ohun ìríra. 12 Ohun ìríra ni gbogbo ohun tó wà nínú omi tí kò ní lẹ́bẹ́ àti ìpẹ́ jẹ́ fún yín.
13 “‘Àwọn ẹ̀dá tó ń fò tí ẹ máa kà sí ohun ìríra nìyí; ẹ ò gbọ́dọ̀ jẹ wọ́n, torí ohun ìríra ni wọ́n jẹ́: ẹyẹ idì,+ idì ajẹja, igún dúdú,+ 14 àwòdì pupa àti gbogbo onírúurú àwòdì dúdú, 15 gbogbo onírúurú ẹyẹ ìwò, 16 ògòǹgò, òwìwí, ẹyẹ àkẹ̀ àti gbogbo onírúurú àṣáǹwéwé, 17 òwìwí kékeré, ẹyẹ àgò, òwìwí elétí gígùn, 18 ògbùgbú, ẹyẹ òfú, igún, 19 ẹyẹ àkọ̀, gbogbo onírúurú ẹyẹ wádòwádò, àgbìgbò àti àdán. 20 Kí gbogbo ẹ̀dá abìyẹ́ tó ń gbá yìn-ìn,* tí wọ́n ń fi ẹsẹ̀ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin rìn jẹ́ ohun ìríra fún yín.
21 “‘Nínú àwọn ẹ̀dá abìyẹ́ tó ń gbá yìn-ìn, tó ń fi ẹsẹ̀ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin rìn, àwọn tó ní tete lókè ẹsẹ̀ wọn láti máa fi tọ lórí ilẹ̀ nìkan ni ẹ lè jẹ. 22 Èyí tí ẹ lè jẹ nínú wọn nìyí: onírúurú eéṣú tó máa ń ṣí kiri, àwọn eéṣú míì tó ṣeé jẹ,+ ìrẹ̀ àti tata. 23 Gbogbo ẹ̀dá abìyẹ́ yòókù tó ń gbá yìn-ìn, tó ní ẹsẹ̀ mẹ́rin jẹ́ ohun ìríra fún yín. 24 Ẹ lè fi nǹkan wọ̀nyí sọ ara yín di aláìmọ́. Gbogbo ẹni tó bá fara kan òkú wọn yóò di aláìmọ́ títí di alẹ́.+ 25 Kí ẹnikẹ́ni tó bá gbé òkú èyíkéyìí lára wọn fọ aṣọ rẹ̀;+ onítọ̀hún yóò di aláìmọ́ títí di alẹ́.
26 “‘Ẹranko èyíkéyìí tí pátákò rẹ̀ là, àmọ́ tí kò sí àlàfo ní pátákò rẹ̀, tí kì í sì í jẹ àpọ̀jẹ, yóò jẹ́ aláìmọ́ fún yín. Gbogbo ẹni tó bá fara kàn wọ́n yóò di aláìmọ́.+ 27 Gbogbo ohun alààyè tó ń fi àtẹ́lẹsẹ̀ rìn nínú àwọn ohun tó ń fi ẹsẹ̀ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin rìn yóò jẹ́ aláìmọ́ fún yín. Gbogbo ẹni tó bá fara kan òkú wọn yóò di aláìmọ́ títí di alẹ́. 28 Kí ẹni tó bá gbé òkú wọn fọ aṣọ rẹ̀,+ yóò sì di aláìmọ́ títí di alẹ́.+ Aláìmọ́ ni wọ́n jẹ́ fún yín.
29 “‘Àwọn ẹ̀dá tó ń rákò lórí ilẹ̀, tó jẹ́ aláìmọ́ fún yín nìyí: ẹ̀lírí, eku,+ gbogbo onírúurú aláǹgbá, 30 ọmọńlé, awọ́nríwọ́n, aláàmù, ọlọ́yọ̀ọ́ǹbẹ́rẹ́ àti ọ̀gà. 31 Aláìmọ́+ ni àwọn ẹ̀dá tó ń rákò yìí jẹ́ fún yín. Gbogbo ẹni tó bá fara kan òkú wọn yóò di aláìmọ́ títí di alẹ́.+
32 “‘Tí wọ́n bá kú, ohunkóhun tí wọ́n bá já bọ́ lé yóò di aláìmọ́, ì báà jẹ́ ohun èlò onígi, aṣọ, awọ tàbí aṣọ ọ̀fọ̀.* Kí ẹ ri ohun èlò èyíkéyìí tí ẹ bá lò bọnú omi, yóò sì di aláìmọ́ títí di alẹ́; lẹ́yìn náà, ó máa mọ́. 33 Tí wọ́n bá já bọ́ sínú ohun èlò tí wọ́n fi amọ̀ ṣe, kí ẹ fọ́ ọ túútúú, ohunkóhun tó bá sì wà nínú rẹ̀ yóò di aláìmọ́.+ 34 Tí omi tó wà nínú ohun èlò náà bá kan oúnjẹ èyíkéyìí, yóò di aláìmọ́. Ohun mímu èyíkéyìí tó bá sì wà nínú ohun èlò náà yóò di aláìmọ́. 35 Ohunkóhun tí òkú wọn bá já bọ́ lé yóò di aláìmọ́. Ì báà jẹ́ ààrò tàbí àdògán kékeré, ṣe ni kí ẹ fọ́ ọ túútúú. Wọ́n ti di aláìmọ́, aláìmọ́ ni wọ́n sì máa jẹ́ fún yín. 36 Ìsun omi àti kòtò omi nìkan ni yóò máa jẹ́ mímọ́, àmọ́ ẹnikẹ́ni tó bá fara kan òkú wọn yóò di aláìmọ́. 37 Tí òkú wọn bá já bọ́ sórí irúgbìn tí ẹ fẹ́ gbìn, irúgbìn náà ṣì jẹ́ mímọ́. 38 Àmọ́ tí ẹ bá da omi sórí irúgbìn kan, tí apá kan lára òkú wọn sì já bọ́ sórí rẹ̀, aláìmọ́ ni irúgbìn náà jẹ́ fún yín.
39 “‘Tí ẹranko tí ẹ máa ń jẹ bá kú, ẹnikẹ́ni tó bá fara kan òkú rẹ̀ yóò di aláìmọ́ títí di alẹ́.+ 40 Kí ẹnikẹ́ni tó bá jẹ lára òkú rẹ̀ fọ aṣọ rẹ̀, yóò sì di aláìmọ́ títí di alẹ́. Kí ẹnikẹ́ni tó bá gbé òkú rẹ̀ fọ aṣọ rẹ̀, yóò sì di aláìmọ́ títí di alẹ́.+ 41 Gbogbo ẹ̀dá tó ń gbá yìn-ìn ní ayé jẹ́ ohun ìríra.+ Ẹ ò gbọ́dọ̀ jẹ wọ́n. 42 Ẹ ò gbọ́dọ̀ jẹ ẹran èyíkéyìí tó ń fi àyà fà, ẹran èyíkéyìí tó ń fi ẹsẹ̀ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin rìn tàbí èyíkéyìí nínú àwọn ẹ̀dá tó ń gbá yìn-ìn ní ayé, tí wọ́n ní ẹsẹ̀ púpọ̀, torí ohun ìríra+ ni wọ́n jẹ́. 43 Ẹ má fi ẹ̀dá èyíkéyìí tó ń gbá yìn-ìn kó ìríra bá ara yín,* ẹ má fi wọ́n kó èérí bá ara yín, kí ẹ má bàa di aláìmọ́.+ 44 Torí èmi ni Jèhófà Ọlọ́run yín,+ ẹ gbọ́dọ̀ ya ara yín sí mímọ́, kí ẹ sì di mímọ́,+ torí mo jẹ́ mímọ́.+ Torí náà, ẹ ò gbọ́dọ̀ fi ẹ̀dá èyíkéyìí tó ń gbá yìn-ìn lórí ilẹ̀ sọ ara yín* di aláìmọ́. 45 Torí èmi ni Jèhófà, tó mú yín kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì láti jẹ́ kí ẹ mọ̀ pé èmi ni Ọlọ́run,+ ẹ gbọ́dọ̀ jẹ́ mímọ́,+ torí èmi jẹ́ mímọ́.+
46 “‘Èyí ni òfin tó wà nípa àwọn ẹranko, àwọn ẹ̀dá tó ń fò, gbogbo ohun alààyè* tó wà nínú omi àti gbogbo ẹ̀dá* tó ń gbá yìn-ìn ní ayé, 47 láti fi ìyàtọ̀ sáàárín èyí tí kò mọ́ àti èyí tó mọ́, sáàárín àwọn ohun alààyè tí ẹ lè jẹ àti àwọn tí ẹ ò gbọ́dọ̀ jẹ.’”+
12 Jèhófà ń bá ọ̀rọ̀ tó ń sọ fún Mósè lọ pé: 2 “Sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé, ‘Tí obìnrin kan bá lóyún,* tó sì bímọ ọkùnrin, ọjọ́ méje ni kí obìnrin náà fi jẹ́ aláìmọ́, bó ṣe jẹ́ ní àwọn ọjọ́ ìdọ̀tí nígbà tó ń ṣe nǹkan oṣù.+ 3 Ní ọjọ́ kẹjọ, kí wọ́n dá adọ̀dọ́+ ọmọkùnrin náà.* 4 Kí obìnrin náà máa wẹ ẹ̀jẹ̀ kúrò lára rẹ̀ fún ọjọ́ mẹ́tàlélọ́gbọ̀n (33) tó tẹ̀ lé e. Kò gbọ́dọ̀ fara kan ohun mímọ́ kankan, kò sì gbọ́dọ̀ wá sínú ibi mímọ́ títí ọjọ́ ìwẹ̀mọ́ rẹ̀ yóò fi pé.
5 “‘Tí ọmọ tó bí bá jẹ́ obìnrin, ọjọ́ mẹ́rìnlá (14) ni kó fi jẹ́ aláìmọ́, bó ṣe máa ń jẹ́ aláìmọ́ tó bá ń ṣe nǹkan oṣù. Kó máa wẹ ẹ̀jẹ̀ kúrò lára rẹ̀ fún ọjọ́ mẹ́rìndínláàádọ́rin (66) tó tẹ̀ lé e. 6 Tí ọjọ́ ìwẹ̀mọ́ rẹ̀ fún ọmọkùnrin tàbí ọmọbìnrin bá pé, kó mú ọmọ àgbò ọlọ́dún kan wá sí ẹnu ọ̀nà àgọ́ ìpàdé fún àlùfáà láti fi rú ẹbọ sísun,+ kó sì mú ọmọ ẹyẹlé tàbí oriri kan wá láti fi rú ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀. 7 Kí àlùfáà mú un wá síwájú Jèhófà, kó ṣe ètùtù fún obìnrin náà, á sì mọ́ kúrò nínú ẹ̀jẹ̀ tó ń dà lára rẹ̀. Èyí ni òfin nípa obìnrin tó bímọ ọkùnrin tàbí obìnrin. 8 Tí agbára rẹ̀ ò bá gbé àgùntàn, kó mú ẹyẹ oriri méjì tàbí ọmọ ẹyẹlé méjì,+ ọ̀kan fún ẹbọ sísun, ìkejì fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, kí àlùfáà ṣe ètùtù fún un, obìnrin náà á sì mọ́.’”
13 Jèhófà wá sọ fún Mósè àti Áárónì pé: 2 “Tí nǹkan kan bá lé sí ara* ẹnì kan, tó sé èépá tàbí tí awọ ara rẹ̀ yọ àbààwọ́n, tó sì lè yọrí sí àrùn ẹ̀tẹ̀*+ ní awọ ara rẹ̀, kí wọ́n mú un wá sọ́dọ̀ àlùfáà Áárónì tàbí ọ̀kan lára àwọn ọmọ rẹ̀ tó jẹ́ àlùfáà.+ 3 Kí àlùfáà yẹ àrùn tó yọ sí ẹni náà lára wò. Tí irun tó wà níbi tí àrùn náà yọ sí bá ti funfun, tó sì rí i pé àrùn náà ti jẹ wọnú kọjá awọ, àrùn ẹ̀tẹ̀ ni. Kí àlùfáà yẹ̀ ẹ́ wò, kó sì kéde pé ẹni náà jẹ́ aláìmọ́. 4 Àmọ́ tí àbààwọ́n tó yọ sí awọ ara onítọ̀hún bá funfun, tó rí i pé kò jẹ wọnú kọjá awọ, tí irun ibẹ̀ kò sì tíì funfun, kí àlùfáà sé ẹni tó ní àrùn náà mọ́lé fún ọjọ́ méje.+ 5 Kí àlùfáà wá yẹ̀ ẹ́ wò ní ọjọ́ keje, tó bá sì rí i pé àrùn náà ti dáwọ́ dúró, tí kò ràn lára rẹ̀, kí àlùfáà tún sé e mọ́lé fún ọjọ́ méje míì.
6 “Kí àlùfáà tún yẹ̀ ẹ́ wò ní ọjọ́ keje, bí àrùn náà bá ti ń lọ, tí kò sì ràn lára rẹ̀, kí àlùfáà kéde pé ẹni náà jẹ́ mímọ́;+ ẹ̀yi lásán ni. Kí ẹni náà wá fọ aṣọ rẹ̀, ẹni náà yóò sì di mímọ́. 7 Àmọ́ tí èépá* náà bá ràn lára rẹ̀ lẹ́yìn tó fara han àlùfáà kí àlùfáà lè kéde pé ó ti di mímọ́, kó tún pa dà lọ fara han àlùfáà náà.* 8 Kí àlùfáà yẹ̀ ẹ́ wò, tí ẹ̀yi náà bá ti ràn lára rẹ̀, kí àlùfáà kéde pé ẹni náà jẹ́ aláìmọ́. Ẹ̀tẹ̀ ni.+
9 “Tí àrùn ẹ̀tẹ̀ bá yọ sí ẹnì kan lára, kí wọ́n mú un wá sọ́dọ̀ àlùfáà, 10 kí àlùfáà sì yẹ̀ ẹ́ wò.+ Tí ohun funfun kan bá wú sí awọ ara rẹ̀, tó ti sọ irun ibẹ̀ di funfun, tí ibi tó wú náà sì ti di egbò,+ 11 àrùn ẹ̀tẹ̀ tó le gan-an ló wà lára rẹ̀ yẹn, kí àlùfáà kéde pé ẹni náà jẹ́ aláìmọ́. Kó má ṣe sé e mọ́lé,+ torí aláìmọ́ ni. 12 Tí ẹ̀tẹ̀ náà bá wá yọ sí gbogbo ara ẹni náà, tó sì bò ó láti orí rẹ̀ dé àtẹ́lẹsẹ̀, níbi tí àlùfáà rí i dé, 13 tí àlùfáà sì ti yẹ̀ ẹ́ wò, tó rí i pé ẹ̀tẹ̀ náà ti bo gbogbo awọ ara rẹ̀, kó kéde pé ẹni tó ní àrùn náà ti di mímọ́.* Gbogbo rẹ̀ ti funfun, ẹni náà sì ti di mímọ́. 14 Àmọ́ nígbàkigbà tí ẹ̀tẹ̀ náà bá di egbò, ẹni náà máa di aláìmọ́. 15 Tí àlùfáà bá ti rí egbò náà, kó kéde pé aláìmọ́+ ni ẹni náà. Egbò náà jẹ́ aláìmọ́. Ẹ̀tẹ̀ ni.+ 16 Àmọ́ tí ojú egbò náà bá tún pa dà di funfun, kí ẹni náà wá sọ́dọ̀ àlùfáà. 17 Kí àlùfáà yẹ̀ ẹ́ wò,+ tí àrùn ara rẹ̀ bá sì ti di funfun, kí àlùfáà kéde pé ẹni tó ní àrùn náà ti di mímọ́. Ẹni náà jẹ́ mímọ́.
18 “Tí eéwo bá yọ sí ẹnì kan lára, tó sì jinná, 19 àmọ́ tí nǹkan funfun kan wú sí ibi tí eéwo náà wà tẹ́lẹ̀ tàbí tí àbààwọ́n tó pọ́n yọ síbẹ̀, kí ẹni náà lọ fi ara rẹ̀ han àlùfáà. 20 Kí àlùfáà yẹ̀ ẹ́ wò,+ tó bá rí i pé ó ti jẹ wọnú kọjá awọ, tí irun ibẹ̀ sì ti funfun, kí àlùfáà kéde pé ẹni náà jẹ́ aláìmọ́. Àrùn ẹ̀tẹ̀ ló yọ lójú eéwo náà. 21 Àmọ́ tí àlùfáà bá yẹ̀ ẹ́ wò, tó sì rí i pé kò sí irun funfun nínú rẹ̀, kò jẹ wọnú kọjá awọ, tó sì ti ń pa rẹ́ lọ, kí àlùfáà sé e mọ́lé fún ọjọ́ méje.+ 22 Tó bá sì hàn kedere pé ó ti ràn lára rẹ̀, kí àlùfáà kéde pé aláìmọ́ ni ẹni náà. Àrùn ni. 23 Àmọ́ tí àbààwọ́n tó yọ níbẹ̀ ò bá kúrò lójú kan, tí kò sì ràn, á jẹ́ pé ojú eéwo yẹn ló kàn fẹ́ wú, kí àlùfáà kéde pé ẹni náà ti di mímọ́.+
24 “Tàbí tí iná bá jó ẹnì kan, tó sì dápàá sí i lára, tí àbààwọ́n tó pọ́n tàbí tó funfun sì wá yọ lójú àpá náà, 25 kí àlùfáà yẹ̀ ẹ́ wò. Tí irun tó wà lójú àbààwọ́n náà bá ti funfun, tó sì rí i pé ó ti jẹ wọnú kọjá awọ, ẹ̀tẹ̀ ló yọ jáde lójú àpá yẹn, kí àlúfáà kéde pé ẹni náà jẹ́ aláìmọ́. Àrùn ẹ̀tẹ̀ ni. 26 Àmọ́ tí àlùfáà bá yẹ̀ ẹ́ wò, tó sì rí i pé kò sí irun funfun níbẹ̀, tí kò jẹ wọnú kọjá awọ, tó sì ti ń pa rẹ́ lọ, kí àlùfáà sé e mọ́lé fún ọjọ́ méje.+ 27 Kí àlùfáà yẹ̀ ẹ́ wò ní ọjọ́ keje, tó bá sì hàn kedere pé ó ti ràn lára rẹ̀, kí àlùfáà kéde pé aláìmọ́ ni ẹni náà. Àrùn ẹ̀tẹ̀ ni. 28 Àmọ́ tí àbààwọ́n tó yọ níbẹ̀ ò bá kúrò lójú kan, tí kò ràn lára rẹ̀, tó sì ń pa rẹ́ lọ, á jẹ́ pé ojú àpá náà ló kàn wú, kí àlùfáà kéde pé ẹni náà jẹ́ mímọ́, torí ojú àpá náà ló wú.
29 “Tí àrùn bá yọ sí ọkùnrin tàbí obìnrin kan ní orí tàbí ní àgbọ̀n, 30 kí àlùfáà yẹ àrùn náà wò.+ Tó bá rí i pé ó jẹ wọnú kọjá awọ, tí irun ibẹ̀ pọ́n fẹ́ẹ́rẹ́fẹ́, tó sì fẹ́lẹ́, kí àlùfáà kéde pé aláìmọ́ ni ẹni náà; ó ti ní àrùn ní awọ orí rẹ̀ tàbí ní àgbọ̀n rẹ̀. Ẹ̀tẹ̀ ló mú un ní orí tàbí ní àgbọ̀n. 31 Àmọ́ tí àlùfáà bá rí i pé àrùn náà ò jẹ wọnú kọjá awọ, tí kò sì sí irun dúdú níbẹ̀, kí àlùfáà sé alárùn náà mọ́lé fún ọjọ́ méje.+ 32 Kí àlùfáà yẹ àrùn náà wò ní ọjọ́ keje, tí kò bá sì tíì ràn, tí kò sí irun tó pọ́n fẹ́ẹ́rẹ́fẹ́ níbẹ̀, tó sì rí i pé àrùn náà ò jẹ wọnú kọjá awọ, 33 kí ẹni náà fá irun rẹ̀, àmọ́ kó má ṣe fá irun tó wà níbi tí àrùn náà ti mú un. Kí àlùfáà wá sé ẹni náà mọ́lé fún ọjọ́ méje.
34 “Kí àlùfáà tún yẹ ibi tí àrùn náà ti mú onítọ̀hún wò ní ọjọ́ keje, tí àrùn tó mú ẹni náà ní awọ orí àti àgbọ̀n ò bá tíì ràn lára rẹ̀, tó sì rí i pé kò jẹ wọnú kọjá awọ, kí àlùfáà kéde pé ẹni náà ti di mímọ́, kó fọ aṣọ rẹ̀, kó sì di mímọ́. 35 Àmọ́ tó bá hàn kedere pé àrùn náà ti ràn lára rẹ̀ lẹ́yìn tí wọ́n kéde pé ó ti di mímọ́, 36 kí àlùfáà tún yẹ̀ ẹ́ wò, tí àrùn náà bá sì ti ràn lára rẹ̀, kí àlùfáà má wulẹ̀ wá irun tó pọ́n fẹ́ẹ́rẹ́fẹ́ níbẹ̀; aláìmọ́ ni ẹni náà. 37 Àmọ́ tó bá yẹ̀ ẹ́ wò, tó rí i pé àrùn náà ò ràn lára rẹ̀, tí irun dúdú sì ti hù níbẹ̀, àrùn náà ti lọ. Ẹni náà mọ́, kí àlùfáà sì kéde pé ó ti di mímọ́.+
38 “Tí àbààwọ́n bá yọ ní awọ ara ọkùnrin tàbí obìnrin kan, tí àbààwọ́n náà sì funfun, 39 kí àlùfáà yẹ̀ ẹ́ wò.+ Tí àbààwọ́n tó yọ sí ara ẹni náà kò bá funfun dáadáa, á jẹ́ pé nǹkan wulẹ̀ sú sí i lára ni, kì í ṣe nǹkan tó léwu. Ẹni náà mọ́.
40 “Tí irun bá re lórí ọkùnrin kan, tó sì párí, ọkùnrin náà mọ́. 41 Tó bá jẹ́ irun iwájú orí rẹ̀ ló re, tí ibẹ̀ sì pá, ẹni náà mọ́. 42 Àmọ́ tí egbò tó pọ́n bá yọ síbi tó pá ní orí rẹ̀ tàbí níwájú orí rẹ̀, ẹ̀tẹ̀ ló yọ sí i lórí tàbí níwájú orí rẹ̀ yẹn. 43 Kí àlùfáà yẹ̀ ẹ́ wò, tí ohun tí àrùn náà mú kó wú sí ibi tó pá ní àtàrí tàbí iwájú orí rẹ̀ bá pọ́n, tó sì jọ ẹ̀tẹ̀ ní awọ ara rẹ̀, 44 adẹ́tẹ̀ ni ẹni náà. Aláìmọ́ ni. Kí àlùfáà kéde rẹ̀ pé aláìmọ́ ni torí àrùn tó mú un ní orí. 45 Ní ti adẹ́tẹ̀ tó ní àrùn náà, kó wọ aṣọ tó ti fà ya, kó má sì tọ́jú irun orí rẹ̀, kó bo irunmú rẹ̀, kó máa ké jáde pé, ‘Aláìmọ́, aláìmọ́!’ 46 Gbogbo ọjọ́ tí àrùn náà bá fi wà lára rẹ̀ ni yóò fi jẹ́ aláìmọ́. Kó lọ máa dá gbé torí pé aláìmọ́ ni. Ẹ̀yìn ibùdó ni kó máa gbé.+
47 “Tí àrùn ẹ̀tẹ̀ bá wà lára aṣọ kan, bóyá aṣọ onírun tàbí aṣọ ọ̀gbọ̀,* 48 ì báà jẹ́ lára òwú tó wà lóròó tàbí èyí tó wà ní ìbú tí wọ́n fi hun aṣọ ọ̀gbọ̀ tàbí aṣọ onírun tàbí lára awọ tàbí ohunkóhun tí wọ́n fi awọ ṣe, 49 tí àbààwọ́n aláwọ̀ ewé tàbí aláwọ̀ pupa tí àrùn náà fà bá wá ran aṣọ, awọ, òwú tó wà lóròó tàbí èyí tó wà ní ìbú tí wọ́n fi hun aṣọ náà, tàbí ohunkóhun tí wọ́n fi awọ ṣe, àrùn ẹ̀tẹ̀ ló ràn án, ó sì yẹ kí ẹ fi han àlùfáà. 50 Kí àlùfáà yẹ àrùn náà wò, kó sì sé ohun tó ní àrùn náà mọ́lé fún ọjọ́ méje.+ 51 Tó bá yẹ àrùn náà wò ní ọjọ́ keje, tó sì rí i pé ó ti ràn lára aṣọ náà, lára òwú tó wà lóròó tàbí èyí tó wà ní ìbú tí wọ́n fi hun aṣọ náà tàbí lára awọ (láìka ohun tí wọ́n ń fi awọ náà ṣe), àrùn ẹ̀tẹ̀ tó le gan-an ni, aláìmọ́+ sì ni. 52 Kó fi iná sun aṣọ náà tàbí òwú tó wà lóròó tàbí èyí tó wà ní ìbú tí wọ́n fi hun aṣọ onírun tàbí aṣọ ọ̀gbọ̀ tàbí ohunkóhun tí wọ́n fi awọ ṣe tí àrùn náà wà lára rẹ̀, torí àrùn ẹ̀tẹ̀ tó le gan-an ni. Kó fi iná sun ún.
53 “Àmọ́ tí àlùfáà bá yẹ̀ ẹ́ wò, tí àrùn náà kò sì tíì ràn lára aṣọ náà, lára òwú tó wà lóròó tàbí èyí tó wà ní ìbú tí wọ́n fi hun aṣọ tàbí lára ohunkóhun tí wọ́n fi awọ ṣe, 54 kí àlùfáà wá pàṣẹ pé kí wọ́n fọ ohun tí àrùn náà wà lára rẹ̀, kó sì sé e mọ́lé fún ọjọ́ méje míì. 55 Kí àlùfáà wá yẹ ohun tí àrùn náà wà lára rẹ̀ wò lẹ́yìn tí wọ́n ti fọ̀ ọ́ dáadáa. Tí ìrísí ibi tí àrùn náà wà kò bá yàtọ̀ sí ti tẹ́lẹ̀, bí àrùn náà ò tiẹ̀ ràn, aláìmọ́ ni. Ṣe ni kí ẹ fi iná sun ún torí ó ti jẹ ní inú tàbí ní ìta.
56 “Àmọ́ tí àlùfáà náà bá yẹ̀ ẹ́ wò, tí ibi tí àrùn náà wà sì ti ń pa rẹ́ lọ lẹ́yìn tí wọ́n ti fọ̀ ọ́ dáadáa, kó ya á kúrò lára aṣọ tàbí awọ tàbí lára òwú tó wà lóròó tàbí èyí tó wà ní ìbú tí wọ́n fi hun aṣọ náà. 57 Àmọ́ tó bá ṣì wà níbòmíì lára aṣọ náà tàbí lára òwú tó wà lóròó tàbí èyí tó wà ní ìbú tí wọ́n fi hun aṣọ náà tàbí ohunkóhun tí wọ́n fi awọ ṣe, ó ti ń ràn nìyẹn, ṣe ni kí ẹ dáná sun ohunkóhun tí àrùn náà bá wà lára rẹ̀.+ 58 Àmọ́ tí ẹ bá fọ aṣọ tàbí òwú tó wà lóròó tàbí èyí tó wà ní ìbú tí wọ́n fi hun aṣọ náà tàbí ohunkóhun tí wọ́n fi awọ ṣe, tí àrùn náà sì kúrò lára rẹ̀, kí ẹ tún un fọ̀ lẹ́ẹ̀kejì, yóò sì di mímọ́.
59 “Èyí ni òfin tí ẹ ó máa tẹ̀ lé tí àrùn ẹ̀tẹ̀ bá wà lára aṣọ onírun tàbí aṣọ ọ̀gbọ̀ tàbí lára òwú tó wà lóròó tàbí èyí tó wà ní ìbú tí wọ́n fi hun aṣọ tàbí lára ohunkóhun tí wọ́n fi awọ ṣe, láti kéde pé ó jẹ́ mímọ́ tàbí pé ó jẹ́ aláìmọ́.”
14 Jèhófà ń bá ọ̀rọ̀ tó ń sọ fún Mósè lọ pé: 2 “Èyí ni òfin tí ẹ ó máa tẹ̀ lé nípa adẹ́tẹ̀, ní ọjọ́ tí àlùfáà máa kéde rẹ̀ pé ó ti di mímọ́, tí wọ́n á sì mú un wá sọ́dọ̀ àlùfáà.+ 3 Kí àlùfáà lọ sí ẹ̀yìn ibùdó, kó sì yẹ̀ ẹ́ wò. Tí àrùn ẹ̀tẹ̀ náà bá ti lọ lára adẹ́tẹ̀ náà, 4 kí àlùfáà pàṣẹ pé kó mú ààyè ẹyẹ méjì tó mọ́ wá, pẹ̀lú igi kédárì, òwú aláwọ̀ rírẹ̀dòdò àti ewéko hísópù láti fi wẹ̀ ẹ́ mọ́.+ 5 Kí àlùfáà pàṣẹ pé kí wọ́n pa ẹyẹ kan nínú ohun èlò tí wọ́n fi amọ̀ ṣe lórí omi tó ń ṣàn. 6 Àmọ́ kó mú ààyè ẹyẹ kejì pẹ̀lú igi kédárì, òwú aláwọ̀ rírẹ̀dòdò àti ewéko hísópù, kó sì kì wọ́n pa pọ̀ bọnú ẹ̀jẹ̀ ẹyẹ tí wọ́n pa lórí omi tó ń ṣàn. 7 Kó wá wọ́n ọn lẹ́ẹ̀méje sára ẹni tó fẹ́ wẹ ara rẹ̀ mọ́ kúrò nínú ẹ̀tẹ̀, kó sì kéde pé ẹni náà ti di mímọ́, kó sì tú ààyè ẹyẹ náà sílẹ̀ lórí pápá gbalasa.+
8 “Kí ẹni tó fẹ́ wẹ ara rẹ̀ mọ́ fọ aṣọ rẹ̀, kó fá gbogbo irun rẹ̀, kó fi omi wẹ̀, yóò sì di mímọ́. Lẹ́yìn náà, ó lè wá sínú ibùdó, àmọ́ ìta àgọ́ rẹ̀ ni kó máa gbé fún ọjọ́ méje. 9 Ní ọjọ́ keje, kó fá gbogbo irun orí rẹ̀ àti àgbọ̀n rẹ̀ àti irun ojú rẹ̀. Tó bá ti fá gbogbo irun rẹ̀, kó fọ aṣọ rẹ̀, kó fi omi wẹ̀, yóò sì di mímọ́.
10 “Ní ọjọ́ kẹjọ, kó mú ọmọ àgbò méjì tí ara wọn dá ṣáṣá, abo ọ̀dọ́ àgùntàn+ ọlọ́dún kan tí ara rẹ̀ dá ṣáṣá, kó mú ìyẹ̀fun tó kúnná tí wọ́n pò mọ́ òróró tó jẹ́ ìdá mẹ́ta nínú mẹ́wàá òṣùwọ̀n eéfà* láti fi ṣe ọrẹ ọkà+ àti òróró tó kún òṣùwọ̀n lọ́ọ̀gì kan;*+ 11 kí àlùfáà tó kéde pé ẹni náà ti di mímọ́ mú ẹni tó fẹ́ wẹ ara rẹ̀ mọ́ náà wá síwájú Jèhófà ní ẹnu ọ̀nà àgọ́ ìpàdé, pẹ̀lú àwọn ọrẹ náà. 12 Kí àlùfáà mú ọmọ àgbò kan, kó fi rú ẹbọ ẹ̀bi+ pẹ̀lú òróró òṣùwọ̀n lọ́ọ̀gì náà, kó sì fì wọ́n síwá-sẹ́yìn bí ọrẹ fífì níwájú Jèhófà.+ 13 Kó wá pa ọmọ àgbò náà níbi tí wọ́n ti máa ń pa ẹran+ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ àti ẹran ẹbọ sísun, ní ibi mímọ́, torí pé àlùfáà ló ni+ ẹbọ ẹ̀bi, bíi ti ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀. Ohun mímọ́ jù lọ ni.+
14 “Kí àlùfáà wá mú lára ẹ̀jẹ̀ ẹbọ ẹ̀bi, kó sì fi sí ìsàlẹ̀ etí ọ̀tún ẹni náà tó fẹ́ wẹ ara rẹ̀ mọ́ àti àtàǹpàkò ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ àti àtàǹpàkò ẹsẹ̀ ọ̀tún rẹ̀. 15 Kí àlùfáà mú lára òróró òṣùwọ̀n lọ́ọ̀gì + náà, kó sì dà á sí àtẹ́lẹwọ́ òsì ara rẹ̀. 16 Kí àlùfáà wá ki ìka ọ̀tún rẹ̀ bọ òróró tó wà ní àtẹ́lẹwọ́ òsì rẹ̀, kó sì fi ìka rẹ̀ wọ́n lára òróró náà lẹ́ẹ̀méje níwájú Jèhófà. 17 Kí àlùfáà wá fi lára òróró tó kù ní àtẹ́lẹwọ́ rẹ̀ sí ìsàlẹ̀ etí ọ̀tún ẹni náà tó fẹ́ wẹ ara rẹ̀ mọ́ àti àtàǹpàkò ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ àti àtàǹpàkò ẹsẹ̀ ọ̀tún rẹ̀ lórí ẹ̀jẹ̀ ẹbọ ẹ̀bi. 18 Kí àlùfáà fi èyí tó ṣẹ́ kù lára òróró tó wà ní àtẹ́lẹwọ́ rẹ̀ sí orí ẹni tó fẹ́ wẹ ara rẹ̀ mọ́, kí àlùfáà sì ṣe ètùtù fún un níwájú Jèhófà.+
19 “Kí àlùfáà rú ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀+ náà, kó sì ṣe ètùtù fún ẹni tó fẹ́ wẹ ara rẹ̀ mọ́ kúrò nínú àìmọ́ rẹ̀, lẹ́yìn náà, kó pa ẹran ẹbọ sísun. 20 Kí àlùfáà sun ẹran ẹbọ sísun àti ọrẹ ọkà+ lórí pẹpẹ, kí àlùfáà sì ṣe ètùtù fún un,+ yóò sì di mímọ́.+
21 “Àmọ́, tó bá jẹ́ aláìní, tí kò sì fi bẹ́ẹ̀ ní lọ́wọ́, kó mú ọmọ àgbò kan láti fi rú ẹbọ ẹ̀bi, kó fi ṣe ọrẹ fífì, kó lè ṣe ètùtù fún ara rẹ̀, pẹ̀lú ìyẹ̀fun tó kúnná, tó jẹ́ ìdá mẹ́wàá òṣùwọ̀n eéfà,* tí wọ́n pò mọ́ òróró láti fi ṣe ọrẹ ọkà, òróró tó kún òṣùwọ̀n lọ́ọ̀gì kan, 22 àti ẹyẹ oriri méjì tàbí ọmọ ẹyẹlé méjì, èyí tí agbára rẹ̀ bá gbé. Ọ̀kan máa jẹ́ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, èkejì á sì jẹ́ ẹbọ sísun.+ 23 Ní ọjọ́ kẹjọ,+ kó mú wọn wá sọ́dọ̀ àlùfáà kó lè kéde pé ó ti di mímọ́ ní ẹnu ọ̀nà àgọ́ ìpàdé níwájú Jèhófà.+
24 “Kí àlùfáà mú ọmọ àgbò tí wọ́n fẹ́ fi rú ẹbọ ẹ̀bi+ náà àti òróró òṣùwọ̀n lọ́ọ̀gì náà, kí àlùfáà sì fì wọ́n síwá-sẹ́yìn bí ọrẹ fífì níwájú Jèhófà.+ 25 Kó wá pa ọmọ àgbò tí wọ́n fẹ́ fi rú ẹbọ ẹ̀bi náà, kí àlùfáà mú lára ẹ̀jẹ̀ ẹran náà, kó sì fi sí ìsàlẹ̀ etí ọ̀tún ẹni náà tó fẹ́ wẹ ara rẹ̀ mọ́ àti àtàǹpàkò ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ àti àtàǹpàkò ẹsẹ̀ ọ̀tún rẹ̀.+ 26 Kí àlùfáà dà lára òróró náà sí àtẹ́lẹwọ́ òsì+ òun fúnra rẹ̀, 27 kó sì fi ìka ọ̀tún rẹ̀ wọ́n lára òróró tó wà ní àtẹ́lẹwọ́ òsì rẹ̀ lẹ́ẹ̀méje níwájú Jèhófà. 28 Kí àlùfáà fi lára òróró tó wà ní àtẹ́lẹwọ́ rẹ̀ sí ìsàlẹ̀ etí ọ̀tún ẹni tó fẹ́ wẹ ara rẹ̀ mọ́ àti àtàǹpàkò ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ àti àtàǹpàkò ẹsẹ̀ ọ̀tún rẹ̀ ní àwọn ibì kan náà tó fi ẹ̀jẹ̀ ẹbọ ẹ̀bi sí. 29 Kí àlùfáà wá fi èyí tó ṣẹ́ kù lára òróró tó wà ní àtẹ́lẹwọ́ rẹ̀ sórí ẹni tó fẹ́ wẹ ara rẹ̀ mọ́, láti ṣe ètùtù fún un níwájú Jèhófà.
30 “Kó fi ọ̀kan lára àwọn ẹyẹ oriri náà tàbí ọ̀kan lára àwọn ọmọ ẹyẹlé náà rúbọ, èyí tí agbára rẹ̀ bá gbé,+ 31 tí apá rẹ̀ ká, kó fi rú ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, kó sì fi èkejì rú ẹbọ sísun+ pẹ̀lú ọrẹ ọkà; kí àlùfáà sì ṣe ètùtù fún ẹni tó fẹ́ wẹ ara rẹ̀ mọ́ níwájú Jèhófà.+
32 “Èyí ni òfin tó wà fún ẹni tó ní àrùn ẹ̀tẹ̀ àmọ́ tí kò ní lọ́wọ́ nígbà tí wọ́n fẹ́ kéde rẹ̀ pé ó ti di mímọ́.”
33 Jèhófà wá sọ fún Mósè àti Áárónì pé: 34 “Tí ẹ bá dé ilẹ̀ Kénáánì+ tí màá fún yín láti fi ṣe ohun ìní,+ tí mo sì jẹ́ kí àrùn ẹ̀tẹ̀+ yọ lára ilé kan ní ilẹ̀ yín, 35 kí ẹni tó ni ilé náà wá sọ fún àlùfáà pé, ‘Àrùn kan ti yọ sára ilé mi.’ 36 Kí àlùfáà pàṣẹ pé kí wọ́n kó gbogbo ohun tó wà nínú ilé náà jáde kó tó wá yẹ àrùn náà wò, kó má bàa kéde pé aláìmọ́ ni gbogbo ohun tó wà nínú ilé náà; lẹ́yìn náà, kí àlùfáà wọlé wá yẹ ilé náà wò. 37 Kó yẹ ibi tí àrùn náà wà wò, tí àwọn ibi tó jìn wọnú, tó ní àwọ̀ ewé tàbí àwọ̀ pupa bá wà lára ògiri ilé náà, tó sì rí i pé ibẹ̀ jẹ wọnú lára ògiri náà, 38 kí àlùfáà jáde kúrò nínú ilé náà lọ sí ẹnu ọ̀nà rẹ̀, kó sì ti ilé náà pa fún ọjọ́ méje.+
39 “Kí àlùfáà pa dà wá yẹ̀ ẹ́ wò ní ọjọ́ keje. Tí àrùn náà bá ti ràn lára ògiri ilé náà, 40 kí àlùfáà pàṣẹ pé kí wọ́n yọ àwọn òkúta tí àrùn náà wà lára wọn kúrò, kí wọ́n sì jù ú sí ẹ̀yìn ìlú níbi àìmọ́. 41 Kó wá mú kí wọ́n ha inú ilé náà dáadáa, kí wọ́n sì da ohun tí wọ́n fi rẹ́ ilé àti àpòrọ́ tí wọ́n ha lára rẹ̀ sí ẹ̀yìn ìlú níbi àìmọ́. 42 Lẹ́yìn náà, kí wọ́n fi àwọn òkúta míì rọ́pò àwọn tí wọ́n yọ kúrò, kó lo àpòrọ́ míì, kó sì ní kí wọ́n tún ilé náà rẹ́.
43 “Àmọ́ tí àrùn náà bá pa dà, tó sì tún yọ lára ilé náà lẹ́yìn tí wọ́n yọ àwọn òkúta, tí wọ́n ha ara ilé náà, tí wọ́n sì tún un rẹ́, 44 kí àlùfáà wọlé lọ yẹ̀ ẹ́ wò. Tí àrùn náà bá ti ràn nínú ilé náà, á jẹ́ pé àrùn ẹ̀tẹ̀ tó le gan-an+ ló wà nínú ilé náà. Ilé náà ti di aláìmọ́. 45 Lẹ́yìn náà, kó ní kí wọ́n wó ilé náà lulẹ̀, tòun ti àwọn òkúta rẹ̀, àwọn ẹ̀là gẹdú àti gbogbo ohun tí wọ́n fi rẹ́ ilé náà àti àpòrọ́ rẹ̀, kó sì ní kí wọ́n kó o lọ sí ẹ̀yìn ìlú, níbi àìmọ́.+ 46 Àmọ́ tí ẹnikẹ́ni bá wọnú ilé náà ní èyíkéyìí nínú àwọn ọjọ́ tí wọ́n fi ti ilé náà pa,+ kí ẹni náà jẹ́ aláìmọ́ títí di alẹ́;+ 47 kí ẹnikẹ́ni tó bá dùbúlẹ̀ sínú ilé náà fọ aṣọ rẹ̀, kí ẹnikẹ́ni tó bá sì jẹun nínú ilé náà fọ aṣọ rẹ̀.
48 “Àmọ́ tí àlùfáà bá wá, tó sì rí i pé àrùn náà ò ràn nínú ilé náà lẹ́yìn tí wọ́n tún un rẹ́, kí àlùfáà kéde pé ilé náà mọ́, torí àrùn náà ti lọ. 49 Kó lè wẹ ẹ̀gbin* kúrò nínú ilé náà, kó mú ẹyẹ méjì, igi kédárì, òwú aláwọ̀ rírẹ̀dòdò àti ewéko hísópù.+ 50 Kó pa ẹyẹ kan nínú ohun èlò tí wọ́n fi amọ̀ ṣe lórí omi tó ń ṣàn. 51 Kó wá mú igi kédárì náà, ewéko hísópù, òwú aláwọ̀ rírẹ̀dòdò àti ààyè ẹyẹ náà, kó rì wọ́n bọnú ẹ̀jẹ̀ ẹyẹ tó pa, kó sì rì wọ́n bọnú omi tó ń ṣàn náà, kó wá wọ́n ọn sára ilé náà lẹ́ẹ̀méje.+ 52 Kó fi ẹ̀jẹ̀ ẹyẹ náà, omi tó ń ṣàn, ààyè ẹyẹ, igi kédárì, ewéko hísópù àti òwú aláwọ̀ rírẹ̀dòdò wẹ ẹ̀gbin* kúrò nínú ilé náà. 53 Kó wá tú ààyè ẹyẹ náà sílẹ̀ ní ẹ̀yìn ìlú náà, lórí pápá gbalasa, kó sì ṣe ètùtù fún ilé náà, ilé náà yóò sì di mímọ́.
54 “Èyí ni òfin nípa àrùn ẹ̀tẹ̀ èyíkéyìí, àrùn tó mú èèyàn ní awọ orí tàbí àgbọ̀n,+ 55 ẹ̀tẹ̀ tó wà lára aṣọ+ tàbí lára ilé,+ 56 àti nípa ohun tó bá wú síni lára, èépá àti àbààwọ́n tó yọ síni lára,+ 57 láti pinnu ohun tó bá jẹ́ aláìmọ́ àti èyí tó jẹ́ mímọ́.+ Èyí ni òfin nípa àrùn ẹ̀tẹ̀.”+
15 Jèhófà ń bá ọ̀rọ̀ tó ń sọ fún Mósè àti Áárónì lọ pé: 2 “Sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé, ‘Tí ohun kan bá ń dà jáde látinú ẹ̀yà ìbímọ* ọkùnrin kan, ohun náà ti sọ ọ́ di aláìmọ́.+ 3 Ohun tó ń dà jáde lára rẹ̀ ti sọ ọ́ di aláìmọ́, yálà ó ṣì ń dà látinú ẹ̀yà ìbímọ rẹ̀ tàbí ibẹ̀ ti dí, aláìmọ́ ṣì ni.
4 “‘Ibùsùn èyíkéyìí tí ẹni tí ohun kan ń dà jáde lára rẹ̀ bá dùbúlẹ̀ sí yóò di aláìmọ́, ohunkóhun tó bá sì jókòó lé yóò di aláìmọ́. 5 Kí ẹni tó bá fara kan ibùsùn rẹ̀ fọ aṣọ rẹ̀, kó fi omi wẹ̀, kó sì jẹ́ aláìmọ́ títí di alẹ́.+ 6 Kí ẹnikẹ́ni tó bá jókòó sórí ohun tí ẹni tí nǹkan ń dà jáde lára rẹ̀ jókòó lé fọ aṣọ rẹ̀, kó fi omi wẹ̀, kó sì jẹ́ aláìmọ́ títí di alẹ́. 7 Kí ẹnikẹ́ni tó bá fara kan ara ẹni tí nǹkan ń dà jáde lára rẹ̀ fọ aṣọ rẹ̀, kó fi omi wẹ̀, kó sì jẹ́ aláìmọ́ títí di alẹ́. 8 Tí ẹni tí nǹkan ń dà jáde lára rẹ̀ bá tutọ́ sára ẹni tó mọ́, kí ẹni náà fọ aṣọ rẹ̀, kó fi omi wẹ̀, kó sì jẹ́ aláìmọ́ títí di alẹ́. 9 Tí ẹni tí nǹkan ń dà jáde lára rẹ̀ bá jókòó sórí ohun tí wọ́n fi ń jókòó tí wọ́n ń dè mọ́ ẹran, ìjókòó náà máa di aláìmọ́. 10 Ẹnikẹ́ni tó bá fara kan ohunkóhun tí onítọ̀hún jókòó lé yóò jẹ́ aláìmọ́ títí di alẹ́, kí ẹnikẹ́ni tó bá sì gbé àwọn nǹkan yẹn fọ aṣọ rẹ̀, kó fi omi wẹ̀, kó sì jẹ́ aláìmọ́ títí di alẹ́. 11 Tí ẹni tí nǹkan ń dà jáde lára rẹ̀+ ò bá tíì fi omi fọ ọwọ́ rẹ̀, tó wá fọwọ́ kan ẹnì kan, kí ẹni náà fọ aṣọ rẹ̀, kó fi omi wẹ̀, kó sì jẹ́ aláìmọ́ títí di alẹ́. 12 Tí ẹni tí nǹkan ń dà jáde lára rẹ̀ bá fara kan ohun èlò tí wọ́n fi amọ̀ ṣe, kí ẹ fọ́ ohun èlò náà túútúú, kí ẹ sì fi omi fọ ohun èlò èyíkéyìí tí wọ́n fi igi ṣe.+
13 “‘Tí ohun tó ń dà náà bá dáwọ́ dúró, tí ẹni náà sì wá mọ́ kúrò nínú rẹ̀, kí ó ka ọjọ́ méje, lẹ́yìn náà kó di mímọ́, kó fọ aṣọ rẹ̀, kó fi omi wẹ̀, yóò sì di mímọ́.+ 14 Ní ọjọ́ kẹjọ, kó mú ẹyẹ oriri méjì tàbí ọmọ ẹyẹlé+ méjì, kó wá síwájú Jèhófà ní ẹnu ọ̀nà àgọ́ ìpàdé, kó sì kó wọn fún àlùfáà. 15 Kí àlùfáà sì fi wọ́n rúbọ, kó fi ọ̀kan rú ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, kó fi èkejì rú ẹbọ sísun, kí àlùfáà sì ṣe ètùtù fún un níwájú Jèhófà torí ohun tó ń dà jáde lára rẹ̀.
16 “‘Tí ọkùnrin kan bá da àtọ̀, kó fi omi wẹ gbogbo ara rẹ̀, kó sì jẹ́ aláìmọ́ títí di alẹ́.+ 17 Kó fi omi fọ aṣọ èyíkéyìí àti awọ èyíkéyìí tí àtọ̀ bá dà sí, kí ohun náà sì jẹ́ aláìmọ́ títí di alẹ́.
18 “‘Tí ọkùnrin kan bá bá obìnrin kan sùn, tó sì da àtọ̀, kí wọ́n fi omi wẹ̀, kí wọ́n sì jẹ́ aláìmọ́ títí di alẹ́.+
19 “‘Tí ẹ̀jẹ̀ bá ń dà jáde lára obìnrin kan, kó ṣì jẹ́ aláìmọ́ nínú ìdọ̀tí nǹkan oṣù rẹ̀ fún ọjọ́ méje.+ Ẹnikẹ́ni tó bá fara kàn án yóò jẹ́ aláìmọ́ títí di alẹ́.+ 20 Ohunkóhun tó bá dùbúlẹ̀ lé nígbà tó bá ń ṣe nǹkan oṣù yóò di aláìmọ́, gbogbo ohun tó bá sì jókòó lé yóò di aláìmọ́.+ 21 Kí ẹnikẹ́ni tó bá fara kan ibùsùn rẹ̀ fọ aṣọ rẹ̀, kó fi omi wẹ̀, kó sì jẹ́ aláìmọ́ títí di alẹ́. 22 Kí ẹnikẹ́ni tó bá fara kan ohunkóhun tí obìnrin náà jókòó lé fọ aṣọ rẹ̀, kó fi omi wẹ̀, kó sì jẹ́ aláìmọ́ títí di alẹ́. 23 Tí obìnrin náà bá jókòó sórí ibùsùn tàbí ohunkóhun míì, ẹni tó bá fara kan ohun náà máa jẹ́ aláìmọ́ títí di alẹ́.+ 24 Tí ọkùnrin kan bá bá a sùn, tí ìdọ̀tí nǹkan oṣù rẹ̀ sì kàn án lára,+ ọkùnrin náà máa jẹ́ aláìmọ́ fún ọjọ́ méje, ibùsùn èyíkéyìí tí ọkùnrin náà bá sì dùbúlẹ̀ sí yóò di aláìmọ́.
25 “‘Tí ẹ̀jẹ̀ bá ń dà lára obìnrin kan fún ọ̀pọ̀ ọjọ́,+ tó sì jẹ́ pé àkókò tó máa ń rí nǹkan oṣù rẹ̀ kò tíì tó+ tàbí tí iye ọjọ́ tí ẹ̀jẹ̀ fi dà lára rẹ̀ bá pọ̀ ju iye tó máa ń jẹ́ tó bá ń ṣe nǹkan oṣù, aláìmọ́ ni yóò jẹ́ ní gbogbo ọjọ́ tí ẹ̀jẹ̀ bá fi ń dà lára rẹ̀, bí ìgbà tó ń ṣe nǹkan oṣù. 26 Ibùsùn èyíkéyìí tó bá dùbúlẹ̀ sí nígbà tí ẹ̀jẹ̀ ń dà lára rẹ̀ yóò dà bí ibùsùn tó dùbúlẹ̀ sí nígbà nǹkan oṣù rẹ̀,+ ohunkóhun tó bá sì jókòó lé yóò di aláìmọ́ bíi ti àìmọ́ nǹkan oṣù rẹ̀. 27 Ẹnikẹ́ni tó bá fara kàn wọ́n yóò di aláìmọ́, kó fọ aṣọ rẹ̀, kó fi omi wẹ̀, kó sì jẹ́ aláìmọ́ títí di alẹ́.+
28 “‘Àmọ́, tí ohun tó ń dà lára rẹ̀ bá ti dáwọ́ dúró, kó ka ọjọ́ méje, lẹ́yìn náà kó di mímọ́.+ 29 Ní ọjọ́ kẹjọ, kó mú ẹyẹ oriri méjì tàbí ọmọ ẹyẹlé+ méjì, kó sì mú wọn wá fún àlùfáà ní ẹnu ọ̀nà àgọ́ ìpàdé.+ 30 Kí àlùfáà fi ọ̀kan rú ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, kó fi èkejì rú ẹbọ sísun. Kí àlùfáà sì ṣe ètùtù fún obìnrin náà níwájú Jèhófà torí ohun àìmọ́ tó ń jáde lára rẹ̀.+
31 “‘Bí o ṣe máa ya àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sọ́tọ̀ kúrò nínú àìmọ́ wọn nìyẹn, kí wọ́n má bàa kú nínú àìmọ́ wọn torí wọ́n sọ àgọ́ ìjọsìn mi tó wà láàárín wọn+ di ẹlẹ́gbin.
32 “‘Èyí ni òfin nípa ọkùnrin tí ohun kan bá ń dà lára rẹ̀, ọkùnrin tó di aláìmọ́ torí àtọ̀ dà lára rẹ̀,+ 33 obìnrin tó ń ṣe nǹkan oṣù,+ ọkùnrin tàbí obìnrin èyíkéyìí tí nǹkan ń dà lára rẹ̀+ àti ọkùnrin tó bá obìnrin tó jẹ́ aláìmọ́ sùn.’”
16 Jèhófà bá Mósè sọ̀rọ̀ lẹ́yìn tí àwọn ọmọ Áárónì méjì kú torí wọ́n lọ síwájú Jèhófà.+ 2 Jèhófà sọ fún Mósè pé: “Sọ fún Áárónì ẹ̀gbọ́n rẹ pé kó má kàn wá sínú ibi mímọ́+ tó wà lẹ́yìn aṣọ ìdábùú+ nígbàkigbà, níwájú ìbòrí Àpótí, kó má bàa kú,+ torí màá fara hàn nínú ìkùukùu*+ lórí ìbòrí+ náà.
3 “Ohun tí Áárónì máa mú wá tó bá ń bọ̀ wá sínú ibi mímọ́ nìyí: ọmọ akọ màlúù láti fi rú ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀+ àti àgbò láti fi rú ẹbọ sísun.+ 4 Kó wọ ẹ̀wù mímọ́ tí wọ́n fi aṣọ ọ̀gbọ̀*+ ṣe, kó sì wọ ṣòkòtò péńpé*+ tí wọ́n fi aṣọ ọ̀gbọ̀ ṣe láti bo ara* rẹ̀, kó de ọ̀já+ tí wọ́n fi aṣọ ọ̀gbọ̀ ṣe mọ́ra, kó sì wé láwàní+ tí wọ́n fi aṣọ ọ̀gbọ̀ ṣe sórí. Aṣọ mímọ́+ ni wọ́n. Kó fi omi wẹ̀,+ kó sì wọ àwọn aṣọ náà.
5 “Kó mú òbúkọ méjì tó ṣì kéré látinú àpéjọ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì+ láti fi rú ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, kó sì fi àgbò kan rú ẹbọ sísun.
6 “Kí Áárónì mú akọ màlúù ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ wá, èyí tó jẹ́ tirẹ̀, kó sì ṣe ètùtù torí ara rẹ̀+ àti ilé rẹ̀.
7 “Kó mú ewúrẹ́ méjèèjì, kó sì mú kí wọ́n dúró síwájú Jèhófà ní ẹnu ọ̀nà àgọ́ ìpàdé. 8 Kí Áárónì ṣẹ́ kèké lórí ewúrẹ́ méjèèjì, kèké kan fún Jèhófà, kèké kejì fún Ásásélì.* 9 Ewúrẹ́ tí kèké+ mú fún Jèhófà ni kí Áárónì mú wá, kó sì fi rú ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀. 10 Àmọ́ kó mú ewúrẹ́ tí kèké mú fún Ásásélì wá láàyè láti dúró níwájú Jèhófà kó lè ṣe ètùtù lórí rẹ̀, kó sì rán an lọ sínú aginjù+ fún Ásásélì.
11 “Kí Áárónì mú akọ màlúù ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ wá, èyí tó jẹ́ tirẹ̀, kó sì ṣe ètùtù torí ara rẹ̀ àti ilé rẹ̀; lẹ́yìn náà, kó pa akọ màlúù ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, tó jẹ́ tirẹ̀.+
12 “Kó wá mú ìkóná+ tí ẹyin iná tó ń jó látorí pẹpẹ+ níwájú Jèhófà kún inú rẹ̀, pẹ̀lú ẹ̀kúnwọ́ tùràrí onílọ́fínńdà+ méjì tó dáa, kó sì kó wọn wá sẹ́yìn aṣọ ìdábùú.+ 13 Kó tún fi tùràrí sínú iná níwájú Jèhófà,+ èéfín tùràrí yóò sì bo ìbòrí Àpótí+ náà, èyí tó wà lórí Ẹ̀rí,+ kó má bàa kú.
14 “Kó mú lára ẹ̀jẹ̀+ akọ màlúù náà, kó fi ìka rẹ̀ wọ́n ọn síwájú ìbòrí náà ní apá ìlà oòrùn, kó sì fi ìka rẹ̀ wọ́n lára ẹ̀jẹ̀ náà lẹ́ẹ̀méje síwájú ìbòrí+ náà.
15 “Kó wá pa ewúrẹ́ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, tó jẹ́ ti àwọn èèyàn,+ kó mú ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ wá sẹ́yìn aṣọ ìdábùú,+ kó sì fi ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ ṣe ohun kan náà tó fi ẹ̀jẹ̀+ akọ màlúù náà ṣe; kó wọ́n ọn sí apá ibi tí ìbòrí náà wà, níwájú ìbòrí náà.
16 “Kó ṣe ètùtù fún ibi mímọ́ torí ìwà àìmọ́ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì àti àṣìṣe wọn àti ẹ̀ṣẹ̀ wọn,+ bẹ́ẹ̀ náà ni kó ṣe fún àgọ́ ìpàdé, èyí tó wà láàárín wọn, láàárín àwọn tó ń hùwà àìmọ́.
17 “Ẹnì kankan ò gbọ́dọ̀ sí nínú àgọ́ ìpàdé látìgbà tó bá ti wọlé lọ ṣe ètùtù ní ibi mímọ́ títí yóò fi jáde. Kó ṣe ètùtù fún ara rẹ̀ àti ilé rẹ̀+ àti gbogbo ìjọ Ísírẹ́lì.+
18 “Kó wá jáde wá síbi pẹpẹ+ tó wà níwájú Jèhófà, kó ṣe ètùtù fún un, kó sì mú lára ẹ̀jẹ̀ akọ màlúù náà àti lára ẹ̀jẹ̀ ewúrẹ́ náà, kó wá fi sára àwọn ìwo tó wà ní gbogbo ẹ̀gbẹ́ pẹpẹ. 19 Kó tún fi ìka rẹ̀ wọ́n lára ẹ̀jẹ̀ náà sára pẹpẹ lẹ́ẹ̀méje, kó lè wẹ̀ ẹ́ mọ́, kó sì sọ ọ́ di mímọ́ kúrò nínú ìwà àìmọ́ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.
20 “Tó bá ti ṣe ètùtù+ fún ibi mímọ́ náà tán, pẹ̀lú àgọ́ ìpàdé àti pẹpẹ,+ kó tún mú ààyè ewúrẹ́+ náà wá. 21 Kí Áárónì gbé ọwọ́ rẹ̀ méjèèjì lé orí ààyè ewúrẹ́ náà, kó jẹ́wọ́ gbogbo àṣìṣe àwọn ọmọ Ísírẹ́lì àti gbogbo ìṣìnà wọn àti gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ wọn sórí rẹ̀, kí ó kó o lé orí ewúrẹ́+ náà, kó wá yan ẹnì kan* tó máa rán ewúrẹ́ náà lọ sínú aginjù. 22 Kí ewúrẹ́ náà fi orí rẹ̀ ru gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ wọn+ lọ sí aṣálẹ̀,+ kó sì rán ewúrẹ́ náà lọ sínú aginjù.+
23 “Kí Áárónì wá wọnú àgọ́ ìpàdé, kó bọ́ ẹ̀wù tí wọ́n fi aṣọ ọ̀gbọ̀ ṣe, èyí tó wọ̀ nígbà tó lọ sínú ibi mímọ́, kó sì kó wọn sílẹ̀ níbẹ̀. 24 Kó fi omi wẹ+ ara rẹ̀* ní ibi mímọ́, kó sì wọ aṣọ rẹ̀;+ kó wá jáde, kó sì rú ẹbọ sísun+ rẹ̀ àti ẹbọ sísun+ àwọn èèyàn náà, kó ṣe ètùtù fún ara rẹ̀ àti fún àwọn èèyàn náà.+ 25 Kó mú kí ọ̀rá ẹran tó fi rúbọ ẹ̀ṣẹ̀ rú èéfín lórí pẹpẹ.
26 “Kí ẹni tó rán ewúrẹ́ náà lọ fún Ásásélì+ fọ aṣọ rẹ̀, kó fi omi wẹ̀, lẹ́yìn náà ó lè wá sínú ibùdó.
27 “Ní ti akọ màlúù ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ àti ewúrẹ́ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, tó mú ẹ̀jẹ̀ wọn wá sínú ibi mímọ́ láti fi ṣe ètùtù, kí ó kó wọn lọ sí ẹ̀yìn ibùdó, kó fi iná sun+ awọ wọn, ẹran wọn àti ìgbẹ́ wọn. 28 Kí ẹni tó fi iná sun ún fọ aṣọ rẹ̀, kó fi omi wẹ̀, lẹ́yìn náà ó lè wá sínú ibùdó.
29 “Àṣẹ tó máa wà fún yín títí lọ ni: Ní ọjọ́ kẹwàá, oṣù keje, kí ẹ pọ́n ara yín* lójú, ẹ ò gbọ́dọ̀ ṣe iṣẹ́ kankan,+ ì báà jẹ́ ọmọ ìbílẹ̀ tàbí àjèjì tó ń gbé láàárín yín. 30 Ọjọ́ yìí ni wọ́n á ṣe ètùtù+ fún yín láti kéde pé ẹ jẹ́ mímọ́. Ẹ máa di mímọ́ kúrò nínú gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ yín níwájú Jèhófà.+ 31 Yóò jẹ́ sábáàtì fún yín, ọjọ́ ìsinmi tí ẹ ò ní ṣiṣẹ́ rárá, kí ẹ sì pọ́n ara yín* lójú.+ Àṣẹ tó máa wà títí lọ ni.
32 “Kí àlùfáà tí ẹ fòróró yàn,+ tí ẹ fiṣẹ́ lé lọ́wọ́* láti ṣe àlùfáà+ dípò bàbá rẹ̀+ ṣe ètùtù, kó sì wọ aṣọ ọ̀gbọ̀,+ aṣọ mímọ́.+ 33 Kó ṣe ètùtù fún ibi mímọ́,+ àgọ́ ìpàdé+ àti pẹpẹ;+ kó sì ṣe ètùtù fún àwọn àlùfáà àti gbogbo ìjọ+ náà. 34 Èyí máa jẹ́ àṣẹ tí ẹ ó máa pa mọ́ títí lọ,+ láti ṣe ètùtù fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lẹ́ẹ̀kan lọ́dún+ torí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ wọn.”
Torí náà, ó ṣe ohun tí Jèhófà pa láṣẹ fún Mósè gẹ́lẹ́.
17 Jèhófà ń bá ọ̀rọ̀ tó ń sọ fún Mósè lọ pé: 2 “Sọ fún Áárónì àti àwọn ọmọ rẹ̀ àti gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé, ‘Ohun tí Jèhófà pa láṣẹ nìyí:
3 “‘“Tí ọkùnrin kankan ní ilé Ísírẹ́lì bá pa akọ màlúù tàbí ọmọ àgbò tàbí ewúrẹ́ nínú ibùdó tàbí tó pa á ní ẹ̀yìn ibùdó, 4 dípò kó mú un wá sí ẹnu ọ̀nà àgọ́ ìpàdé láti fi ṣe ọrẹ fún Jèhófà níwájú àgọ́ ìjọsìn Jèhófà, ọkùnrin náà máa jẹ̀bi ẹ̀jẹ̀. Ó ti ta ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀, ṣe ni kí ẹ pa á, kí ẹ lè mú un kúrò láàárín àwọn èèyàn rẹ̀. 5 Èyí máa mú kí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì mú ẹbọ wọn, tí wọ́n ń rú nínú pápá gbalasa wá fún Jèhófà, sí ẹnu ọ̀nà àgọ́ ìpàdé, sọ́dọ̀ àlùfáà. Kí wọ́n fi nǹkan wọ̀nyí rúbọ bí ẹbọ ìrẹ́pọ̀ sí Jèhófà.+ 6 Kí àlùfáà wọ́n ẹ̀jẹ̀ ẹran náà sórí pẹpẹ Jèhófà ní ẹnu ọ̀nà àgọ́ ìpàdé, kó sì mú kí ọ̀rá ẹran náà rú èéfín sí Jèhófà láti mú òórùn dídùn* jáde.+ 7 Torí náà, kí wọ́n má ṣe rú ẹbọ mọ́ sí àwọn ẹ̀mí èṣù tó rí bí ewúrẹ́,*+ èyí tí wọ́n ń bá ṣèṣekúṣe.+ Kí èyí jẹ́ àṣẹ tó máa wà títí lọ fún yín, jálẹ̀ àwọn ìran yín.”’
8 “Kí o sọ fún wọn pé, ‘Tí ọkùnrin kankan ní ilé Ísírẹ́lì tàbí tí àjèjì kankan tó ń gbé láàárín yín bá rú ẹbọ sísun tàbí tó rúbọ, 9 tí kò sì mú un wá sí ẹnu ọ̀nà àgọ́ ìpàdé láti fi rúbọ sí Jèhófà, kí ẹ pa ẹni náà, kí ẹ lè mú un kúrò láàárín àwọn èèyàn rẹ̀.+
10 “‘Tí ọkùnrin kankan ní ilé Ísírẹ́lì tàbí tí àjèjì kankan tó ń gbé láàárín yín bá jẹ ẹ̀jẹ̀+ èyíkéyìí, ó dájú pé mi ò ní fi ojú rere wo ẹni* tó ń jẹ ẹ̀jẹ̀, èmi yóò sì pa á, kí n lè mú un kúrò láàárín àwọn èèyàn rẹ̀. 11 Torí inú ẹ̀jẹ̀+ ni ẹ̀mí* ẹran wà, èmi fúnra mi sì ti fi sórí pẹpẹ+ fún yín kí ẹ lè ṣe ètùtù fún ara yín,* torí ẹ̀jẹ̀ ló ń ṣe ètùtù+ nípasẹ̀ ẹ̀mí* tó wà nínú rẹ̀. 12 Ìdí nìyẹn tí mo fi sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé: “Ìkankan* nínú yín ò gbọ́dọ̀ jẹ ẹ̀jẹ̀, àjèjì kankan tó ń gbé láàárín yín+ ò sì gbọ́dọ̀ jẹ ẹ̀jẹ̀.”+
13 “‘Tí ọmọ Ísírẹ́lì kan tàbí àjèjì kan tó ń gbé láàárín yín bá ń ṣọdẹ, tó sì mú ẹran ìgbẹ́ tàbí ẹyẹ tí ẹ lè jẹ, ó gbọ́dọ̀ da ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ jáde,+ kó sì fi erùpẹ̀ bò ó. 14 Torí ẹ̀jẹ̀ ni ẹ̀mí* gbogbo onírúurú ẹran, torí pé ẹ̀mí* wà nínú ẹ̀jẹ̀ náà. Ìdí nìyẹn tí mo fi sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé: “Ẹ ò gbọ́dọ̀ jẹ ẹ̀jẹ̀ ẹran èyíkéyìí, torí ẹ̀jẹ̀ ni ẹ̀mí* gbogbo onírúurú ẹran. Kí ẹ pa ẹnikẹ́ni tó bá jẹ ẹ́.”+ 15 Tí ẹnikẹ́ni* bá jẹ òkú ẹran tàbí èyí tí ẹran inú igbó fà ya,+ ì báà jẹ́ ọmọ ìbílẹ̀ tàbí àjèjì ló jẹ ẹ́, kó fọ aṣọ rẹ̀, kó fi omi wẹ̀, kó sì di aláìmọ́ títí di alẹ́;+ lẹ́yìn náà, á di mímọ́. 16 Àmọ́ tí kò bá fọ̀ wọ́n, tí kò sì wẹ̀,* yóò jìyà ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀.’”+
18 Jèhófà ń bá ọ̀rọ̀ tó ń sọ fún Mósè lọ pé: 2 “Sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé, ‘Èmi ni Jèhófà Ọlọ́run yín.+ 3 Ẹ ò gbọ́dọ̀ ṣe bí wọ́n ṣe ń ṣe nílẹ̀ Íjíbítì tí ẹ gbé rí, ẹ ò sì gbọ́dọ̀ ṣe bí wọ́n ṣe ń ṣe nílẹ̀ Kénáánì tí mò ń mú yín lọ.+ Ẹ ò gbọ́dọ̀ tẹ̀ lé àṣẹ wọn. 4 Kí ẹ máa tẹ̀ lé àwọn ìdájọ́ mi, kí ẹ máa pa àwọn àṣẹ mi mọ́, kí ẹ sì máa rìn nínú wọn.+ Èmi ni Jèhófà Ọlọ́run yín. 5 Kí ẹ máa pa àwọn àṣẹ mi àti àwọn ìdájọ́ mi mọ́; yóò mú kí ẹnikẹ́ni tó bá ń pa á mọ́ wà láàyè.+ Èmi ni Jèhófà.
6 “‘Ẹnikẹ́ni nínú yín ò gbọ́dọ̀ sún mọ́ ìkankan nínú àwọn mọ̀lẹ́bí rẹ̀ tó sún mọ́ ọn láti bá a lò pọ̀.*+ Èmi ni Jèhófà. 7 O ò gbọ́dọ̀ bá bàbá rẹ lò pọ̀, o ò gbọ́dọ̀ bá ìyá rẹ lò pọ̀. Ìyá rẹ ni, o ò sì gbọ́dọ̀ bá a lò pọ̀.
8 “‘O ò gbọ́dọ̀ bá ìyàwó bàbá rẹ lò pọ̀.+ Ìyẹn máa dójú ti bàbá rẹ.*
9 “‘O ò gbọ́dọ̀ bá arábìnrin rẹ lò pọ̀, ì báà jẹ́ ọmọ bàbá rẹ tàbí ọmọ ìyá rẹ, ì báà jẹ́ agbo ilé kan náà ni wọ́n bí yín sí tàbí bẹ́ẹ̀ kọ́.+
10 “‘O ò gbọ́dọ̀ bá ọmọbìnrin tí ọmọ rẹ ọkùnrin bí lò pọ̀ tàbí kí o bá ọmọbìnrin tí ọmọ rẹ obìnrin bí lò pọ̀, torí ìhòòhò rẹ ni wọ́n.
11 “‘O ò gbọ́dọ̀ bá ọmọbìnrin tí ìyàwó bàbá rẹ bí lò pọ̀, torí ọmọ bàbá kan náà lẹ jẹ́, arábìnrin rẹ ni.
12 “‘O ò gbọ́dọ̀ bá arábìnrin bàbá rẹ lò pọ̀. Mọ̀lẹ́bí bàbá rẹ tímọ́tímọ́ ni.+
13 “‘O ò gbọ́dọ̀ bá arábìnrin ìyá rẹ lò pọ̀, torí mọ̀lẹ́bí ìyá rẹ tímọ́tímọ́ ni.
14 “‘O ò gbọ́dọ̀ bá ìyàwó arákùnrin bàbá rẹ lò pọ̀, kí o má bàa dójú ti* arákùnrin bàbá rẹ. Ìyàwó arákùnrin bàbá rẹ ni.+
15 “‘O ò gbọ́dọ̀ bá ìyàwó ọmọ rẹ lò pọ̀.+ Ìyàwó ọmọ rẹ ni, o ò gbọ́dọ̀ bá a lò pọ̀.
16 “‘O ò gbọ́dọ̀ bá ìyàwó arákùnrin rẹ lò pọ̀,+ torí ìyẹn máa dójú ti arákùnrin rẹ.*
17 “‘O ò gbọ́dọ̀ bá ìyá àti ọmọbìnrin rẹ̀ lò pọ̀.+ O ò gbọ́dọ̀ mú ọmọbìnrin tí ọmọ rẹ̀ ọkùnrin bí tàbí ọmọbìnrin tí ọmọ rẹ̀ obìnrin bí kí o lè bá a lò pọ̀. Mọ̀lẹ́bí rẹ̀ tímọ́tímọ́ ni wọ́n, ìwà àìnítìjú* ni.
18 “‘O ò gbọ́dọ̀ fẹ́ arábìnrin ìyàwó rẹ láti fi ṣe orogún rẹ̀,+ o ò sì gbọ́dọ̀ bá a lò pọ̀ nígbà tí arábìnrin rẹ̀ ṣì wà láàyè.
19 “‘O ò gbọ́dọ̀ sún mọ́ obìnrin nígbà tó bá ń ṣe nǹkan oṣù rẹ̀ láti bá a lò pọ̀.+
20 “‘O ò gbọ́dọ̀ bá ìyàwó ẹnì kejì rẹ* lò pọ̀ kí o wá tipa bẹ́ẹ̀ sọ ara rẹ di aláìmọ́.+
21 “‘O ò gbọ́dọ̀ jẹ́ kí wọ́n fi ìkankan nínú àwọn ọmọ rẹ rúbọ sí* Mólékì.+ O ò gbọ́dọ̀ tipa bẹ́ẹ̀ sọ orúkọ Ọlọ́run rẹ di aláìmọ́.+ Èmi ni Jèhófà.
22 “‘O ò gbọ́dọ̀ bá ọkùnrin sùn bí ìgbà tí ò ń bá obìnrin sùn.+ Ohun ìríra ni.
23 “‘Ọkùnrin ò gbọ́dọ̀ bá ẹranko lò pọ̀, kó má bàa di aláìmọ̀; obìnrin ò sì gbọ́dọ̀ jẹ́ kí ẹranko bá òun lò pọ̀.+ Kì í ṣe ìwà tó tọ́.
24 “‘Ẹ má fi èyíkéyìí nínú àwọn nǹkan yìí sọ ara yín di aláìmọ́, torí gbogbo àwọn nǹkan yìí ni àwọn orílẹ̀-èdè tí mo fẹ́ lé kúrò níwájú yín fi sọ ara wọn di aláìmọ́.+ 25 Torí náà, ilẹ̀ náà jẹ́ aláìmọ́, màá fìyà ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ jẹ ẹ́, ilẹ̀ náà yóò sì pọ àwọn tó ń gbé ibẹ̀ jáde.+ 26 Àmọ́ kí ẹ̀yin fúnra yín máa pa àwọn àṣẹ mi àti àwọn ìlànà mi mọ́,+ ẹ ò sì gbọ́dọ̀ ṣe ìkankan nínú àwọn ohun ìríra yìí, ì báà jẹ́ ọmọ ìbílẹ̀ tàbí àjèjì tó ń gbé láàárín yín.+ 27 Torí gbogbo ohun ìríra wọ̀nyí ni àwọn tó gbé ilẹ̀ náà ṣáájú yín+ ti ṣe, ilẹ̀ náà sì ti wá di aláìmọ́. 28 Kí ilẹ̀ náà má bàa pọ̀ yín jáde torí pé ẹ sọ ọ́ di ẹlẹ́gbin, bó ṣe máa pọ àwọn orílẹ̀-èdè tó wà ṣáájú yín jáde. 29 Tí ẹnikẹ́ni bá ṣe èyíkéyìí nínú àwọn ohun ìríra yìí, kí ẹ pa gbogbo àwọn* tó bá ń ṣe é, kí ẹ lè mú wọn kúrò láàárín àwọn èèyàn wọn. 30 Kí ẹ máa ṣe ohun tí mo pa láṣẹ fún yín, ẹ ò gbọ́dọ̀ lọ́wọ́ sí àṣà èyíkéyìí tó ń ríni lára tí wọ́n ṣe ṣáájú yín,+ kí ẹ má bàa fi wọ́n sọ ara yín di aláìmọ́. Èmi ni Jèhófà Ọlọ́run yín.’”
19 Jèhófà wá sọ fún Mósè pé: 2 “Sọ fún gbogbo àpéjọ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé, ‘Kí ẹ jẹ́ mímọ́, torí èmi Jèhófà Ọlọ́run yín jẹ́ mímọ́.+
3 “‘Kí kálukú yín máa bọ̀wọ̀ fún* ìyá rẹ̀ àti bàbá rẹ̀,+ kí ẹ sì máa pa àwọn sábáàtì+ mi mọ́. Èmi ni Jèhófà Ọlọ́run yín. 4 Ẹ má ṣe yíjú sí àwọn ọlọ́run tí kò ní láárí+ tàbí kí ẹ fi irin rọ àwọn ọlọ́run+ fún ara yín. Èmi ni Jèhófà Ọlọ́run yín.
5 “‘Tí ẹ bá rú ẹbọ ìrẹ́pọ̀ sí Jèhófà,+ kí ẹ rú ẹbọ náà lọ́nà tí ẹ ó fi rí ìtẹ́wọ́gbà.+ 6 Kí ẹ jẹ ẹ́ ní ọjọ́ tí ẹ bá rúbọ àti ní ọjọ́ kejì, àmọ́ kí ẹ fi iná sun+ èyí tó bá ṣẹ́ kù di ọjọ́ kẹta. 7 Tí ẹ bá jẹ èyíkéyìí nínú rẹ̀ ní ọjọ́ kẹta, ohun tí kò tọ́ lẹ ṣe, kò sì ní rí ìtẹ́wọ́gbà. 8 Ẹni tó bá jẹ ẹ́ yóò jìyà ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, torí ó ti sọ ohun mímọ́ Jèhófà di aláìmọ́, ṣe ni kí ẹ pa ẹni* náà, kí ẹ lè mú un kúrò láàárín àwọn èèyàn rẹ̀.
9 “‘Tí ẹ bá ń kórè oko yín, ẹ ò gbọ́dọ̀ kárúgbìn eteetí oko yín tán, ẹ ò sì gbọ́dọ̀ pèéṣẹ́* irè oko yín.+ 10 Bákan náà, ẹ ò gbọ́dọ̀ kó àwọn ohun tó ṣẹ́ kù sílẹ̀ nínú ọgbà àjàrà yín tàbí kí ẹ ṣa àwọn èso àjàrà tó fọ́n ká sínú ọgbà àjàrà yín. Ẹ fi í sílẹ̀ fún àwọn aláìní*+ àti àjèjì. Èmi ni Jèhófà Ọlọ́run yín.
11 “‘Ẹ ò gbọ́dọ̀ jalè,+ ẹ ò gbọ́dọ̀ tanni jẹ,+ ẹ ò sì gbọ́dọ̀ hùwà àìṣòótọ́ sí ara yín. 12 Ẹ ò gbọ́dọ̀ fi orúkọ mi búra èké,+ kí ẹ má bàa sọ orúkọ Ọlọ́run yín di aláìmọ́. Èmi ni Jèhófà. 13 Ẹ ò gbọ́dọ̀ lu ọmọnìkejì yín ní jìbìtì,+ ẹ ò sì gbọ́dọ̀ jalè.+ Owó iṣẹ́ alágbàṣe ò gbọ́dọ̀ wà lọ́wọ́ yín di àárọ̀ ọjọ́ kejì.+
14 “‘Ẹ ò gbọ́dọ̀ ṣépè fún* adití tàbí kí ẹ fi ohun ìdènà síwájú afọ́jú,+ ẹ sì gbọ́dọ̀ máa bẹ̀rù Ọlọ́run yín.+ Èmi ni Jèhófà.
15 “‘Ẹ ò gbọ́dọ̀ yí ìdájọ́ po. Ẹ ò gbọ́dọ̀ rẹ́ aláìní jẹ tàbí kí ẹ ṣe ojúsàájú sí ọlọ́rọ̀.+ Máa ṣe ìdájọ́ òdodo tí o bá ń dá ẹjọ́ ẹnì kejì rẹ.
16 “‘O ò gbọ́dọ̀ máa bani lórúkọ jẹ́ káàkiri láàárín àwọn èèyàn rẹ.+ O ò gbọ́dọ̀ dìde lòdì sí ẹ̀mí* ẹnì kejì rẹ.*+ Èmi ni Jèhófà.
17 “‘O ò gbọ́dọ̀ kórìíra arákùnrin rẹ nínú ọkàn rẹ.+ Kí o rí i pé o bá ẹnì kejì rẹ wí,+ kí o má bàa jẹ nínú ìyà ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀.
18 “‘O ò gbọ́dọ̀ gbẹ̀san+ tàbí kí o di ọmọ àwọn èèyàn rẹ sínú, o sì gbọ́dọ̀ nífẹ̀ẹ́ ọmọnìkejì rẹ bí ara rẹ.+ Èmi ni Jèhófà.
19 “‘Kí ẹ máa pa àwọn àṣẹ mi mọ́: Ẹ ò gbọ́dọ̀ mú kí oríṣi ẹran ọ̀sìn yín méjì bá ara wọn lò pọ̀. Ẹ ò gbọ́dọ̀ gbin oríṣi irúgbìn méjì sínú oko yín,+ ẹ ò sì gbọ́dọ̀ wọ aṣọ tó ní oríṣi òwú méjì tí wọ́n hun pọ̀.+
20 “‘Tí ọkùnrin kan bá dùbúlẹ̀ ti obìnrin kan, tó sì bá a lò pọ̀, tó sì jẹ́ pé ìránṣẹ́ ọkùnrin míì ni obìnrin náà, àmọ́ tí wọn ò tíì rà á pa dà tàbí dá a sílẹ̀, ẹ gbọ́dọ̀ fìyà jẹ wọ́n. Àmọ́, ẹ má pa wọ́n, torí wọn ò tíì dá obìnrin náà sílẹ̀. 21 Kí ọkùnrin náà mú ẹbọ ẹ̀bi rẹ̀ wá fún Jèhófà ní ẹnu ọ̀nà àgọ́ ìpàdé, àgbò kan fún ẹbọ ẹ̀bi.+ 22 Kí àlùfáà fi àgbò ẹbọ ẹ̀bi náà ṣe ètùtù fún un níwájú Jèhófà torí ẹ̀ṣẹ̀ tó dá, yóò sì rí ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ gbà.
23 “‘Tí ẹ bá dé ilẹ̀ náà, tí ẹ sì gbin igi èyíkéyìí fún oúnjẹ, kí ẹ ka èso rẹ̀ sí ohun àìmọ́ àti èèwọ̀.* Ọdún mẹ́ta ni yóò fi jẹ́ èèwọ̀* fún yín. Ẹ ò gbọ́dọ̀ jẹ ẹ́. 24 Àmọ́ ní ọdún kẹrin, gbogbo èso rẹ̀ yóò di ohun mímọ́ láti fi yọ̀ níwájú Jèhófà.+ 25 Tó bá di ọdún karùn-ún, ẹ lè jẹ èso rẹ̀, kí ohun tí ẹ máa kórè lè pọ̀ sí i. Èmi ni Jèhófà Ọlọ́run yín.
26 “‘Ẹ ò gbọ́dọ̀ jẹ ohunkóhun tòun ti ẹ̀jẹ̀ rẹ̀.+
“‘Ẹ ò gbọ́dọ̀ woṣẹ́, ẹ ò sì gbọ́dọ̀ pidán.+
27 “‘Ẹ ò gbọ́dọ̀ fá* irun ẹ̀gbẹ́ orí yín tàbí kí ẹ ba eteetí irùngbọ̀n yín jẹ́.+
28 “‘Ẹ ò gbọ́dọ̀ kọ ara yín lábẹ torí ẹni tó kú,*+ ẹ ò sì gbọ́dọ̀ fín àmì sí ara yín. Èmi ni Jèhófà.
29 “‘Má ba ọmọbìnrin rẹ jẹ́ nípa sísọ ọ́ di aṣẹ́wó,+ kí ilẹ̀ náà má bàa ṣiṣẹ́ aṣẹ́wó, kí ìwà ìbàjẹ́+ sì kún ibẹ̀.
30 “‘Ẹ gbọ́dọ̀ máa pa àwọn sábáàtì mi mọ́,+ kí ẹ sì máa bọ̀wọ̀ fún* ibi mímọ́ mi. Èmi ni Jèhófà.
31 “‘Ẹ má tọ àwọn abẹ́mìílò lọ.+ Ẹ má sì wádìí ọ̀rọ̀ lọ́wọ́ àwọn woṣẹ́woṣẹ́,+ kí wọ́n má bàa sọ yín di aláìmọ́. Èmi ni Jèhófà Ọlọ́run yín.
32 “‘Kí o dìde níwájú orí ewú,+ kí o máa bọlá fún àgbàlagbà,+ kí o sì máa bẹ̀rù Ọlọ́run+ rẹ. Èmi ni Jèhófà.
33 “‘Tí àjèjì kan bá ń gbé pẹ̀lú yín ní ilẹ̀ yín, ẹ ò gbọ́dọ̀ fìyà jẹ ẹ́.+ 34 Kí ẹ máa ṣe àjèjì tó ń bá yín gbé bí ọmọ ìbílẹ̀;+ kí ẹ nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ bí ara yín, torí àjèjì lẹ jẹ́ ní ilẹ̀ Íjíbítì.+ Èmi ni Jèhófà Ọlọ́run yín.
35 “‘Ẹ ò gbọ́dọ̀ lo ìwọ̀n èké tí ẹ bá ń díwọ̀n bí ohun kan ṣe gùn tó, bó ṣe wúwo tó tàbí bó ṣe pọ̀ tó.+ 36 Kí ẹ máa lo òṣùwọ̀n tó péye, ìwọ̀n tó péye, òṣùwọ̀n tó péye fún ohun tí kò lómi* àti òṣùwọ̀n tó péye fún nǹkan olómi.*+ Èmi ni Jèhófà Ọlọ́run yín, ẹni tó mú yín kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì. 37 Torí náà, kí ẹ máa pa gbogbo àṣẹ mi àti gbogbo ìdájọ́ mi mọ́, kí ẹ sì máa tẹ̀ lé wọn.+ Èmi ni Jèhófà.’”
20 Jèhófà ń bá ọ̀rọ̀ tó ń sọ fún Mósè lọ pé: 2 “Sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé, ‘Ẹ gbọ́dọ̀ pa ọmọ Ísírẹ́lì àti àjèjì èyíkéyìí tó ń gbé ní Ísírẹ́lì tó bá fún Mólékì ní ìkankan nínú àwọn ọmọ rẹ̀.+ Kí àwọn èèyàn ilẹ̀ náà sọ ọ́ lókùúta pa. 3 Èmi fúnra mi kò ní fi ojú rere wo ọkùnrin yẹn, màá sì pa á, kí n lè mú un kúrò láàárín àwọn èèyàn rẹ̀, torí ó ti fún Mólékì lára àwọn ọmọ rẹ̀, ó ti sọ ibi mímọ́+ mi di ẹlẹ́gbin, ó sì ti sọ orúkọ mímọ́ mi di aláìmọ́. 4 Tí àwọn èèyàn ilẹ̀ náà bá mọ̀ọ́mọ̀ gbójú fo ohun tí ọkùnrin yẹn ṣe nígbà tó fún Mólékì ní ọmọ rẹ̀, tí wọn ò sì pa á,+ 5 ó dájú pé èmi fúnra mi kò ní fi ojú rere wo ọkùnrin yẹn àti ìdílé rẹ̀.+ Màá pa ọkùnrin náà kí n lè mú un kúrò láàárín àwọn èèyàn rẹ̀, pẹ̀lú gbogbo àwọn tí wọ́n jọ ń bá Mólékì ṣèṣekúṣe.
6 “‘Ní ti ẹni tó bá tọ àwọn abẹ́mìílò+ lọ àti àwọn woṣẹ́woṣẹ́+ kó lè bá wọn ṣe àgbèrè ẹ̀sìn, ó dájú pé màá bínú sí onítọ̀hún,* màá sì pa á, kí n lè mú un kúrò láàárín àwọn èèyàn rẹ̀.+
7 “‘Kí ẹ ya ara yín sí mímọ́, kí ẹ sì di mímọ́,+ torí èmi ni Jèhófà Ọlọ́run yín. 8 Kí ẹ máa pa àwọn àṣẹ mi mọ́, kí ẹ sì máa tẹ̀ lé wọn.+ Èmi ni Jèhófà, ẹni tó ń sọ yín di mímọ́.+
9 “‘Tí ẹnì kan bá wà tó ń ṣépè* fún bàbá tàbí ìyá rẹ̀, ẹ gbọ́dọ̀ pa á.+ Ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ wà lórí òun fúnra rẹ̀, torí ó ti ṣépè fún bàbá tàbí ìyá rẹ̀.
10 “‘Tí ọkùnrin kan bá bá ìyàwó ọkùnrin míì ṣe àgbèrè: Ẹ gbọ́dọ̀ pa ẹni tó bá ìyàwó ẹnì kejì rẹ̀ ṣe àgbèrè, ọkùnrin alágbèrè àti obìnrin alágbèrè náà.+ 11 Ọkùnrin tó bá bá ìyàwó bàbá rẹ̀ sùn ti dójú ti* bàbá rẹ̀.+ Ẹ gbọ́dọ̀ pa àwọn méjèèjì. Ẹ̀jẹ̀ wọn wà lórí wọn. 12 Tí ọkùnrin kan bá bá ìyàwó ọmọ rẹ̀ sùn, ẹ gbọ́dọ̀ pa àwọn méjèèjì. Ohun tí kò tọ́ ni wọ́n ṣe. Ẹ̀jẹ̀ wọn wà lọ́rùn wọn.+
13 “‘Tí ọkùnrin kan bá bá ọkùnrin sùn bí ìgbà tó ń bá obìnrin sùn, ohun ìríra ni àwọn méjèèjì ṣe.+ Ẹ gbọ́dọ̀ pa wọ́n. Ẹ̀jẹ̀ wọn wà lórí wọn.
14 “‘Tí ọkùnrin kan bá bá ìyà àti ọmọ lò pọ̀, ìwà àìnítìjú* ló hù.+ Ṣe ni kí ẹ fi iná sun+ òun pẹ̀lú wọn, kí ìwà àìnítìjú má bàa gbilẹ̀ láàárín yín.
15 “‘Tí ọkùnrin kan bá bá ẹranko lò pọ̀, ẹ gbọ́dọ̀ pa á, kí ẹ sì pa ẹranko náà.+ 16 Tí obìnrin kan bá sì sún mọ́ ẹranko èyíkéyìí láti bá a lò pọ̀,+ ṣe ni kí ẹ pa obìnrin náà àti ẹranko náà. Ẹ gbọ́dọ̀ pa wọ́n. Ẹ̀jẹ̀ wọn wà lọ́rùn wọn.
17 “‘Tí ọkùnrin kan bá bá arábìnrin rẹ̀ tó jẹ́ ọmọ bàbá rẹ̀ tàbí ọmọ ìyá rẹ̀ lò pọ̀, tó rí ìhòòhò obìnrin náà, tí obìnrin náà sì rí ìhòòhò rẹ̀, ohun ìtìjú ni.+ Kí ẹ pa wọ́n níṣojú àwọn ọmọ àwọn èèyàn wọn. Ó ti dójú ti* arábìnrin rẹ̀. Kó jìyà ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀.
18 “‘Tí ọkùnrin kan bá sùn ti obìnrin tó ń ṣe nǹkan oṣù, tó sì bá a lò pọ̀, àwọn méjèèjì ti fi ìsun ẹ̀jẹ̀ obìnrin náà hàn síta.+ Ṣe ni kí ẹ pa àwọn méjèèjì, kí ẹ lè mú wọn kúrò láàárín àwọn èèyàn wọn.
19 “‘O ò gbọ́dọ̀ bá arábìnrin ìyá rẹ tàbí arábìnrin bàbá rẹ lò pọ̀, torí ìyẹn máa dójú ti mọ̀lẹ́bí rẹ tó sún mọ́ ọ.+ Kí wọ́n jìyà ẹ̀ṣẹ̀ wọn. 20 Ọkùnrin tó bá bá ìyàwó arákùnrin òbí rẹ̀ lò pọ̀ ti dójú ti* arákùnrin òbí rẹ̀.+ Kí wọ́n jìyà ẹ̀ṣẹ̀ wọn. Kí wọ́n kú láìbímọ. 21 Tí ọkùnrin kan bá gba ìyàwó arákùnrin rẹ̀, ohun ìríra ni.+ Ó ti dójú ti* arákùnrin rẹ̀. Kí wọ́n di aláìlọ́mọ.
22 “‘Kí ẹ máa pa gbogbo àṣẹ mi àti gbogbo ìdájọ́+ mi mọ́, kí ẹ sì máa tẹ̀ lé wọn,+ kí ilẹ̀ tí màá mú yín lọ láti máa gbé má bàa pọ̀ yín jáde.+ 23 Ẹ ò gbọ́dọ̀ tẹ̀ lé àṣẹ àwọn orílẹ̀-èdè tí màá lé jáde kúrò níwájú yín;+ torí wọ́n ti ṣe gbogbo nǹkan yìí, mo sì kórìíra wọn.+ 24 Ìdí nìyẹn tí mo fi sọ fún yín pé: “Ẹ ó gba ilẹ̀ wọn, màá sì fún yín kó lè di tiyín, ilẹ̀ tí wàrà àti oyin ti ń ṣàn.+ Èmi ni Jèhófà Ọlọ́run yín, ẹni tó yà yín sọ́tọ̀ kúrò lára àwọn èèyàn yòókù.”+ 25 Kí ẹ fi ìyàtọ̀ sáàárín ẹranko tó mọ́ àti èyí tó jẹ́ aláìmọ́ àti sáàárín ẹyẹ tó jẹ́ aláìmọ́ àti èyí tó mọ́;+ ẹ ò gbọ́dọ̀ sọ ara yín* di ohun ìríra nípasẹ̀ ẹranko tàbí ẹyẹ tàbí ohunkóhun tó ń rákò lórí ilẹ̀ tí mo yà sọ́tọ̀ pé ó jẹ́ aláìmọ́ fún yín.+ 26 Kí ẹ jẹ́ mímọ́ fún mi, torí èmi Jèhófà jẹ́ mímọ́,+ mo sì ń yà yín sọ́tọ̀ kúrò lára àwọn èèyàn yòókù kí ẹ lè di tèmi.+
27 “‘Ẹ gbọ́dọ̀ pa ọkùnrin tàbí obìnrin èyíkéyìí tó jẹ́ abẹ́mìílò tàbí woṣẹ́woṣẹ́.*+ Kí àwọn èèyàn sọ wọ́n lókùúta pa. Ẹ̀jẹ̀ wọn wà lórí wọn.’”
21 Jèhófà wá sọ fún Mósè pé: “Sọ fún àwọn àlùfáà, àwọn ọmọ Áárónì pé, ‘Ẹnikẹ́ni nínú yín ò gbọ́dọ̀ sọ ara rẹ̀ di aláìmọ́ torí ẹni* tó kú láàárín àwọn èèyàn rẹ̀.+ 2 Àmọ́ ó lè ṣe bẹ́ẹ̀ tí ẹni náà bá jẹ́ mọ̀lẹ́bí rẹ̀ tó sún mọ́ ọn, ìyá rẹ̀, bàbá rẹ̀, ọmọkùnrin rẹ̀, ọmọbìnrin rẹ̀ tàbí arákùnrin rẹ̀, 3 ó sì lè fi arábìnrin rẹ̀ sọ ara rẹ̀ di aláìmọ́, tó bá jẹ́ wúńdíá tó wà nítòsí rẹ̀, tí kò sì tíì lọ́kọ. 4 Kò gbọ́dọ̀ fi obìnrin tó fẹ́ ọkọ láàárín àwọn èèyàn rẹ̀ sọ ara rẹ̀ di ẹlẹ́gbin tàbí sọ ara rẹ̀ di aláìmọ́. 5 Kí wọ́n má ṣe fá orí wọn,+ kí wọ́n má sì fá eteetí irùngbọ̀n wọn tàbí kí wọ́n fi nǹkan ya ara wọn.+ 6 Kí wọ́n jẹ́ mímọ́ sí Ọlọ́run wọn,+ kí wọ́n má sì sọ orúkọ Ọlọ́run wọn di aláìmọ́,+ torí àwọn ló ń mú àwọn ọrẹ àfinásun sí Jèhófà wá, oúnjẹ* Ọlọ́run wọn, wọ́n gbọ́dọ̀ jẹ́ mímọ́.+ 7 Wọn ò gbọ́dọ̀ fẹ́ aṣẹ́wó,+ obìnrin tí wọ́n ti bá sùn tàbí obìnrin tí ọkọ rẹ̀ kọ̀ sílẹ̀,+ torí àlùfáà jẹ́ mímọ́ sí Ọlọ́run rẹ̀. 8 Kí o sọ ọ́ di mímọ́,+ torí òun ló ń gbé oúnjẹ Ọlọ́run rẹ wá. Kó jẹ́ mímọ́ sí ọ, torí èmi Jèhófà, tó ń sọ yín di mímọ́, jẹ́ mímọ́.+
9 “‘Tí ọmọbìnrin àlùfáà bá ṣe aṣẹ́wó, tó tipa bẹ́ẹ̀ sọ ara rẹ̀ di aláìmọ́, bàbá rẹ̀ ló sọ di aláìmọ́. Kí ẹ fi iná sun+ ọmọbìnrin náà.
10 “‘Ẹni tó jẹ́ àlùfáà àgbà nínú àwọn arákùnrin rẹ̀, tí wọ́n da òróró àfiyanni+ sí lórí, tí wọ́n sì ti fi iṣẹ́ lé lọ́wọ́* kó lè wọ aṣọ àlùfáà,+ kò gbọ́dọ̀ fi orí rẹ̀ sílẹ̀ láìtọ́jú tàbí kó ya aṣọ rẹ̀.+ 11 Kó má ṣe sún mọ́ òkú ẹnikẹ́ni;*+ tó bá tiẹ̀ jẹ́ bàbá rẹ̀ tàbí ìyá rẹ̀, kò gbọ́dọ̀ fi wọ́n sọ ara rẹ̀ di aláìmọ́. 12 Kò gbọ́dọ̀ jáde kúrò nínú ibi mímọ́, kò sì gbọ́dọ̀ sọ ibi mímọ́ Ọlọ́run rẹ̀ di aláìmọ́,+ torí àmì ìyàsímímọ́, òróró àfiyanni ti Ọlọ́run rẹ̀,+ wà lórí rẹ̀. Èmi ni Jèhófà.
13 “‘Obìnrin tó jẹ́ wúńdíá+ ni kó fi ṣe aya. 14 Kó má ṣe fẹ́ opó, obìnrin tí ọkọ rẹ̀ kọ̀ sílẹ̀, ẹni tí wọ́n ti bá sùn tàbí aṣẹ́wó; àmọ́ kó mú wúńdíá látinú àwọn èèyàn rẹ̀, kó fi ṣe aya. 15 Kó má sọ ọmọ* rẹ̀ di aláìmọ́ láàárín àwọn èèyàn rẹ̀,+ torí èmi ni Jèhófà, tó ń sọ ọ́ di mímọ́.’”
16 Jèhófà ń bá ọ̀rọ̀ tó ń sọ fún Mósè lọ pé: 17 “Sọ fún Áárónì pé, ‘Ọkùnrin èyíkéyìí tó bá ní àbùkù lára nínú àwọn ọmọ* rẹ jálẹ̀ àwọn ìran wọn kò gbọ́dọ̀ sún mọ́ tòsí láti gbé oúnjẹ Ọlọ́run rẹ̀ wá. 18 Tí ọkùnrin èyíkéyìí bá ní àbùkù lára, kó má ṣe sún mọ́ tòsí: ọkùnrin tó fọ́jú tàbí tó yarọ tàbí tí ojú rẹ̀ ní àbùkù* tàbí tí apá tàbí ẹsẹ̀ rẹ̀ kan gùn jù, 19 tàbí ọkùnrin tí egungun ẹsẹ̀ rẹ̀ tàbí egungun ọwọ́ rẹ̀ kán, 20 abuké tàbí aràrá* tàbí ọkùnrin tí ojú ń dùn tàbí tó ní ifo tàbí làpálàpá tàbí tí nǹkan ṣe kórópọ̀n rẹ̀.+ 21 Ọkùnrin èyíkéyìí tó ní àbùkù lára nínú àwọn ọmọ* àlùfáà Áárónì ò gbọ́dọ̀ sún mọ́ tòsí láti gbé àwọn ọrẹ àfinásun sí Jèhófà wá. Kò gbọ́dọ̀ sún mọ́ tòsí láti gbé oúnjẹ Ọlọ́run rẹ̀ wá torí ó ní àbùkù lára. 22 Ó lè jẹ oúnjẹ Ọlọ́run rẹ̀, látinú àwọn ohun mímọ́ jù lọ+ àti àwọn ohun mímọ́.+ 23 Àmọ́, kó má ṣe sún mọ́ aṣọ ìdábùú,+ kó má sì sún mọ́ pẹpẹ,+ torí ó ní àbùkù lára; kó má sì sọ ibi mímọ́+ mi di aláìmọ́, torí èmi ni Jèhófà tó ń sọ wọ́n di mímọ́.’”+
24 Mósè sì bá Áárónì àti àwọn ọmọ rẹ̀ àti gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sọ̀rọ̀.
22 Jèhófà tún sọ fún Mósè pé: 2 “Sọ fún Áárónì àti àwọn ọmọ rẹ̀ pé kí wọ́n kíyè sára pẹ̀lú bí wọ́n á ṣe máa ṣe* ohun mímọ́ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, kí wọ́n má sì fi àwọn ohun tí wọ́n ń yà sí mímọ́ fún mi+ sọ orúkọ mímọ́+ mi di aláìmọ́. Èmi ni Jèhófà. 3 Sọ fún wọn pé, ‘Jálẹ̀ àwọn ìran yín, èyíkéyìí nínú àwọn ọmọ yín tó bá ṣì jẹ́ aláìmọ́, tó wá sún mọ́ àwọn ohun mímọ́ tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì yà sí mímọ́ fún Jèhófà, kí ẹ pa ẹni* náà kúrò níwájú mi.+ Èmi ni Jèhófà. 4 Ìkankan nínú àwọn ọmọ Áárónì tó bá jẹ́ adẹ́tẹ̀+ tàbí tí nǹkan ń dà lára rẹ̀+ ò gbọ́dọ̀ jẹ nínú àwọn ohun mímọ́ títí ẹni náà yóò fi di mímọ́,+ bẹ́ẹ̀ náà ni ẹnikẹ́ni tó bá fara kan ẹni tí òkú èèyàn* sọ di aláìmọ́+ tàbí ọkùnrin tó ń da àtọ̀+ 5 tàbí ẹni tó bá fara kan ẹ̀dá tó ń gbá yìn-ìn+ tó jẹ́ aláìmọ́ tàbí tó fara kan ẹnì kan tí ohunkóhun mú kó di aláìmọ́, tó sì lè sọ ọ́ di aláìmọ́.+ 6 Ẹni* tó bá fara kan ìkankan nínú ìwọ̀nyí yóò jẹ́ aláìmọ́ títí di alẹ́, kó má sì jẹ ìkankan nínú àwọn ohun mímọ́, àmọ́ kó fi omi wẹ̀.+ 7 Tí oòrùn bá ti wọ̀, yóò di mímọ́, lẹ́yìn náà, ó lè jẹ nínú àwọn ohun mímọ́, torí oúnjẹ rẹ̀ ni.+ 8 Bákan náà, kò gbọ́dọ̀ jẹ òkú ẹran èyíkéyìí tàbí ohunkóhun tí ẹranko burúkú fà ya, kó sì di aláìmọ́ nípasẹ̀ rẹ̀.+ Èmi ni Jèhófà.
9 “‘Wọ́n gbọ́dọ̀ máa ṣe ojúṣe wọn sí mi, kí wọ́n má bàa tipa bẹ́ẹ̀ ṣẹ̀, kí wọ́n sì kú torí rẹ̀, torí pé wọ́n sọ ọ́ di aláìmọ́. Èmi ni Jèhófà, tó ń sọ wọ́n di mímọ́.
10 “‘Ẹnikẹ́ni tí kò lẹ́tọ̀ọ́ sí* ohunkóhun tó jẹ́ mímọ́ ò gbọ́dọ̀ jẹ ẹ́.+ Àlejò èyíkéyìí tó wà lọ́dọ̀ àlùfáà tàbí alágbàṣe ò gbọ́dọ̀ jẹ ohunkóhun tó jẹ́ mímọ́. 11 Àmọ́ tí àlùfáà bá fi owó rẹ̀ ra ẹnì kan,* ẹni náà lè jẹ nínú rẹ̀. Àwọn ẹrú tí wọ́n bí ní ilé rẹ̀ náà lè jẹ nínú oúnjẹ rẹ̀.+ 12 Tí ọmọbìnrin àlùfáà bá fẹ́ ẹni tí kì í ṣe àlùfáà,* kó má jẹ nínú àwọn ohun mímọ́ tí wọ́n fi ṣe ọrẹ. 13 Àmọ́ tí ọmọbìnrin àlùfáà bá di opó tàbí tí ọkọ rẹ̀ kọ̀ ọ́ sílẹ̀, tí kò sì ní ọmọ, tó sì pa dà sí ilé bàbá rẹ̀ bí ìgbà tó wà léwe, ó lè jẹ nínú oúnjẹ bàbá rẹ̀;+ àmọ́ ẹni tí kò lẹ́tọ̀ọ́ sí i* kò gbọ́dọ̀ jẹ ẹ́.
14 “‘Tí ẹnì kan bá ṣèèṣì jẹ ohun mímọ́, kó fi ìdá márùn-ún rẹ̀ kún un, kó sì fún àlùfáà ní ọrẹ mímọ́ náà.+ 15 Torí náà, kí wọ́n má sọ ohun mímọ́ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tí wọ́n fi ṣe ọrẹ fún Jèhófà di aláìmọ́,+ 16 kí wọ́n sì mú wọn fa ìyà sórí ara wọn torí pé wọ́n jẹ̀bi bí wọ́n ṣe jẹ àwọn ohun mímọ́ wọn; torí èmi ni Jèhófà, ẹni tó ń sọ wọ́n di mímọ́.’”
17 Jèhófà ń bá ọ̀rọ̀ tó ń sọ fún Mósè lọ pé: 18 “Sọ fún Áárónì àti àwọn ọmọ rẹ̀ àti gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé, ‘Tí ọmọ Ísírẹ́lì kan tàbí àjèjì kan ní Ísírẹ́lì bá mú ẹran ẹbọ sísun+ wá fún Jèhófà kó lè fi san ẹ̀jẹ́ rẹ̀ tàbí kó lè fi ṣe ọrẹ àtinúwá,+ 19 akọ ẹran tí ara rẹ̀ dá ṣáṣá+ ni kó mú wá látinú ọ̀wọ́ ẹran, àwọn ọmọ àgbò tàbí àwọn ewúrẹ́ kó lè rí ìtẹ́wọ́gbà. 20 Ẹ ò gbọ́dọ̀ mú ohunkóhun tó ní àbùkù+ wá, torí kò ní mú kí ẹ rí ìtẹ́wọ́gbà.
21 “‘Tí ẹnì kan bá mú ẹran ẹbọ ìrẹ́pọ̀+ wá fún Jèhófà kó lè fi san ẹ̀jẹ́ tàbí kó lè fi ṣe ọrẹ àtinúwá, ẹran tí ara rẹ̀ dá ṣáṣá ni kó mú wá látinú ọ̀wọ́ ẹran tàbí agbo ẹran, kó lè rí ìtẹ́wọ́gbà. Ẹran náà ò gbọ́dọ̀ ní àbùkù kankan. 22 Ẹran tí ẹ fẹ́ fi ṣe ọrẹ ò gbọ́dọ̀ fọ́jú, kò gbọ́dọ̀ kán léegun, kò gbọ́dọ̀ ní ọgbẹ́, èkúrú,* èépá tàbí làpálàpá; ẹ ò gbọ́dọ̀ mú ẹran tó ní èyíkéyìí nínú nǹkan wọ̀nyí wá fún Jèhófà tàbí kí ẹ fi irú rẹ̀ rúbọ lórí pẹpẹ sí Jèhófà. 23 Ẹ lè mú akọ màlúù tàbí àgùntàn tí apá tàbí ẹsẹ̀ rẹ̀ kan kéré jù tàbí tó gùn jù wá, láti fi ṣe ọrẹ àtinúwá, àmọ́ tí ẹ bá mú un wá láti fi san ẹ̀jẹ́, kò ní rí ìtẹ́wọ́gbà. 24 Ẹ má ṣe mú ẹran tí nǹkan ti ṣe kórópọ̀n rẹ̀ wá fún Jèhófà tàbí èyí tí kórópọ̀n rẹ̀ fọ́ tàbí tí wọ́n tẹ̀ lọ́dàá tàbí tí wọ́n gé kórópọ̀n rẹ̀ kúrò, ẹ ò sì gbọ́dọ̀ fi irú àwọn ẹran bẹ́ẹ̀ rúbọ ní ilẹ̀ yín. 25 Ẹ ò gbọ́dọ̀ mú èyíkéyìí nínú àwọn ẹran yìí wá láti ọwọ́ àjèjì láti fi ṣe oúnjẹ Ọlọ́run yín, torí pé wọ́n ní àbùkù, aláàbọ̀ ara sì ni wọ́n. Wọn ò ní rí ìtẹ́wọ́gbà tí ẹ bá mú wọn wá.’”
26 Jèhófà ń bá ọ̀rọ̀ tó ń sọ fún Mósè lọ pé: 27 “Tí màlúù, àgbò tàbí ewúrẹ́ bá bímọ, ọjọ́ méje+ ni kí ọmọ náà fi wà pẹ̀lú ìyá rẹ̀, àmọ́ láti ọjọ́ kẹjọ sókè, tí wọ́n bá fi ṣe ọrẹ, ọrẹ àfinásun sí Jèhófà, ó máa rí ìtẹ́wọ́gbà. 28 Ẹ ò gbọ́dọ̀ pa akọ màlúù tàbí àgùntàn pẹ̀lú ọmọ rẹ̀ ní ọjọ́ kan náà.+
29 “Tí ẹ bá rú ẹbọ ìdúpẹ́ sí Jèhófà,+ kí ẹ rú ẹbọ náà kí ẹ bàa lè rí ìtẹ́wọ́gbà. 30 Ọjọ́ yẹn ni kí ẹ jẹ ẹ́. Ẹ ò gbọ́dọ̀ ṣẹ́ ìkankan lára rẹ̀ kù di àárọ̀ ọjọ́ kejì.+ Èmi ni Jèhófà.
31 “Kí ẹ máa pa àwọn àṣẹ mi mọ́, kí ẹ sì máa tẹ̀ lé wọn.+ Èmi ni Jèhófà. 32 Ẹ ò gbọ́dọ̀ sọ orúkọ mímọ́ mi di aláìmọ́,+ ṣe ni kí ẹ fi hàn pé mo jẹ́ mímọ́ láàárín àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.+ Èmi ni Jèhófà, ẹni tó ń sọ yín di mímọ́,+ 33 ẹni tó mú yín kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì láti jẹ́ kí ẹ mọ̀ pé èmi ni Ọlọ́run.+ Èmi ni Jèhófà.”
23 Jèhófà ń bá ọ̀rọ̀ tó ń sọ fún Mósè lọ pé: 2 “Sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé, ‘Àwọn àjọyọ̀ àtìgbàdégbà+ tó jẹ́ ti Jèhófà tí ẹ máa kéde+ jẹ́ àpéjọ mímọ́. Èyí ni àwọn àjọyọ̀ mi àtìgbàdégbà:
3 “‘Ọjọ́ mẹ́fà ni kí ẹ fi ṣiṣẹ́, àmọ́ kí ọjọ́ keje jẹ́ sábáàtì, tí ẹ ò ní ṣiṣẹ́ rárá,+ kó jẹ́ àpéjọ mímọ́. Ẹ ò gbọ́dọ̀ ṣe iṣẹ́ kankan. Sábáàtì ni kó jẹ́ sí Jèhófà níbikíbi tí ẹ bá ń gbé.+
4 “‘Èyí ni àwọn àjọyọ̀ àtìgbàdégbà tó jẹ́ ti Jèhófà, àwọn àpéjọ mímọ́ tí ẹ máa kéde ní àwọn àkókò tí mo yàn fún wọn: 5 Ìrọ̀lẹ́* ọjọ́ kẹrìnlá oṣù kìíní+ ni kí ẹ ṣe Ìrékọjá+ fún Jèhófà.
6 “‘Ọjọ́ kẹẹ̀ẹ́dógún oṣù yìí ni Àjọyọ̀ Búrẹ́dì Aláìwú+ fún Jèhófà. Ọjọ́ méje ni kí ẹ fi jẹ búrẹ́dì aláìwú.+ 7 Ní ọjọ́ kìíní, kí ẹ ṣe àpéjọ mímọ́.+ Ẹ ò gbọ́dọ̀ ṣiṣẹ́ agbára kankan. 8 Àmọ́ kí ẹ ṣe ọrẹ àfinásun sí Jèhófà fún ọjọ́ méje. Ní ọjọ́ keje, àpéjọ mímọ́ máa wà. Ẹ ò gbọ́dọ̀ ṣe iṣẹ́ agbára kankan.’”
9 Jèhófà ń bá ọ̀rọ̀ tó ń sọ fún Mósè lọ pé: 10 “Sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé, ‘Tí ẹ bá dé ilẹ̀ tí màá fún yín, tí ẹ sì ti kórè oko rẹ̀, kí ẹ mú ìtí àkọ́so+ ìkórè yín wá fún àlùfáà.+ 11 Yóò sì fi ìtí náà síwá-sẹ́yìn níwájú Jèhófà kí ẹ lè rí ìtẹ́wọ́gbà. Ọjọ́ tó tẹ̀ lé sábáàtì ni kí àlùfáà fì í. 12 Ní ọjọ́ tí ẹ bá wá fi ìtí náà, kí ẹ fi ọmọ àgbò ọlọ́dún kan tí ara rẹ̀ dá ṣáṣá rúbọ, kí ẹ fi rú ẹbọ sísun sí Jèhófà. 13 Ọrẹ ọkà rẹ̀ máa jẹ́ ìyẹ̀fun tó kúnná tó jẹ́ ìdá méjì nínú mẹ́wàá òṣùwọ̀n eéfà,* tí wọ́n pò mọ́ òróró, kí ẹ fi ṣe ọrẹ àfinásun sí Jèhófà, tó máa mú òórùn dídùn* jáde. Ọrẹ ohun mímu rẹ̀ máa jẹ́ wáìnì tó kún ìlàrin òṣùwọ̀n hínì.* 14 Ẹ ò gbọ́dọ̀ jẹ búrẹ́dì kankan, ọkà tí wọ́n yan tàbí ọkà tuntun títí di ọjọ́ yìí, títí ẹ ó fi mú ọrẹ Ọlọ́run yín wá. Àṣẹ tí gbogbo ìran yín á máa pa mọ́ títí lọ ni, níbikíbi tí ẹ bá ń gbé.
15 “‘Kí ẹ ka sábáàtì méje láti ọjọ́ tó tẹ̀ lé Sábáàtì, láti ọjọ́ tí ẹ mú ìtí ọrẹ fífì+ náà wá. Kí ọjọ́ àwọn ọ̀sẹ̀ náà pé. 16 Kí ẹ ka àádọ́ta (50) ọjọ́+ títí dé ọjọ́ tó tẹ̀ lé Sábáàtì keje, kí ẹ wá mú ọrẹ ọkà tuntun wá fún Jèhófà.+ 17 Kí ẹ mú ìṣù búrẹ́dì méjì wá láti ibi tí ẹ̀ ń gbé kí ẹ fi ṣe ọrẹ fífì. Ìyẹ̀fun tó kúnná tó jẹ́ ìdá méjì nínú mẹ́wàá òṣùwọ̀n eéfà* ni kí ẹ fi ṣe é. Kí ẹ fi ìwúkàrà sí i,+ kí ẹ sì yan án, kí ẹ fi ṣe àkọ́pọ́n èso fún Jèhófà.+ 18 Kí ẹ mú akọ ọ̀dọ́ àgùntàn méje, tí ọ̀kọ̀ọ̀kan jẹ́ ọlọ́dún kan, tí ara wọn dá ṣáṣá àti ọmọ akọ màlúù kan àti àgbò+ méjì, kí ẹ mú wọn wá pẹ̀lú àwọn búrẹ́dì náà. Kí ẹ fi wọ́n rú ẹbọ sísun sí Jèhófà pẹ̀lú ọrẹ ọkà wọn àti ọrẹ ohun mímu wọn, kó jẹ́ ọrẹ àfinásun sí Jèhófà tó ń mú òórùn dídùn* jáde. 19 Kí ẹ fi ọmọ ewúrẹ́ kan rú ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀,+ kí ẹ sì fi akọ ọ̀dọ́ àgùntàn méjì tí ọ̀kọ̀ọ̀kan jẹ́ ọlọ́dún kan rú ẹbọ ìrẹ́pọ̀.+ 20 Kí àlùfáà fì wọ́n síwá-sẹ́yìn pẹ̀lú àwọn búrẹ́dì tí ẹ fi ṣe àkọ́pọ́n èso, kó fi ṣe ọrẹ fífì níwájú Jèhófà, pẹ̀lú akọ ọ̀dọ́ àgùntàn méjì náà. Kí wọ́n jẹ́ ohun mímọ́ sí Jèhófà fún àlùfáà náà.+ 21 Ní ọjọ́ yìí, kí ẹ kéde+ àpéjọ mímọ́ fún ara yín. Ẹ ò gbọ́dọ̀ ṣe iṣẹ́ agbára kankan. Àṣẹ tí gbogbo ìran yín á máa pa mọ́ títí lọ ni, ní gbogbo ibi tí ẹ̀ ń gbé.
22 “‘Tí ẹ bá kórè oko yín, ẹ ò gbọ́dọ̀ kárúgbìn eteetí oko yín tán, ẹ má sì ṣa ohun tó bá ṣẹ́ kù lẹ́yìn tí ẹ kórè.+ Kí ẹ fi í sílẹ̀ fún àwọn aláìní*+ àti àjèjì.+ Èmi ni Jèhófà Ọlọ́run yín.’”
23 Jèhófà ń bá ọ̀rọ̀ tó ń sọ fún Mósè lọ pé: 24 “Sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé, ‘Ní ọjọ́ kìíní oṣù keje, kí ẹ sinmi, kí ẹ má ṣiṣẹ́ kankan, kí ẹ fi ìró kàkàkí+ kéde rẹ̀ láti máa rántí, yóò jẹ́ àpéjọ mímọ́. 25 Ẹ má ṣiṣẹ́ agbára kankan, kí ẹ sì ṣe ọrẹ àfinásun sí Jèhófà.’”
26 Jèhófà tún sọ fún Mósè pé: 27 “Ọjọ́ kẹwàá oṣù keje yìí ni Ọjọ́ Ètùtù.+ Kí ẹ ṣe àpéjọ mímọ́, kí ẹ pọ́n ara yín* lójú,+ kí ẹ sì ṣe ọrẹ àfinásun sí Jèhófà. 28 Ẹ má ṣe iṣẹ́ kankan ní ọjọ́ yìí gangan, torí ó jẹ́ ọjọ́ ètùtù tí wọ́n á ṣe ètùtù+ fún yín níwájú Jèhófà Ọlọ́run yín. 29 Kí ẹ pa ẹnikẹ́ni* tí kò bá pọ́n ara rẹ̀ lójú* ní ọjọ́ yìí, kí ẹ lè mú un kúrò láàárín àwọn èèyàn rẹ̀.+ 30 Ẹnikẹ́ni* tó bá ṣiṣẹ́ kankan lọ́jọ́ náà, ṣe ni màá pa á run kúrò láàárín àwọn èèyàn rẹ̀. 31 Ẹ ò gbọ́dọ̀ ṣe iṣẹ́ kankan. Àṣẹ tí gbogbo ìran yín á máa pa mọ́ títí lọ ni, níbikíbi tí ẹ bá ń gbé. 32 Sábáàtì ló jẹ́ fún yín, ọjọ́ ìsinmi tí ẹ ò ní ṣiṣẹ́ rárá, kí ẹ sì pọ́n ara yín* lójú+ ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ kẹsàn-án oṣù. Láti ìrọ̀lẹ́ dé ìrọ̀lẹ́ ni kí ẹ máa pa sábáàtì yín mọ́.”
33 Jèhófà ń bá ọ̀rọ̀ tó ń sọ fún Mósè lọ pé: 34 “Sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé, ‘Ọjọ́ kẹẹ̀ẹ́dógún oṣù keje yìí ni Àjọyọ̀ Àtíbàbà fún Jèhófà, ọjọ́ méje ni kí ẹ fi ṣe é.+ 35 Àpéjọ mímọ́ yóò wà ní ọjọ́ kìíní, ẹ ò sì gbọ́dọ̀ ṣe iṣẹ́ agbára kankan. 36 Ọjọ́ méje ni kí ẹ fi ṣe ọrẹ àfinásun sí Jèhófà. Ní ọjọ́ kẹjọ, kí ẹ ṣe àpéjọ mímọ́,+ kí ẹ sì ṣe ọrẹ àfinásun sí Jèhófà. Àpéjọ ọlọ́wọ̀ ni. Ẹ ò gbọ́dọ̀ ṣe iṣẹ́ agbára kankan.
37 “‘Èyí ni àwọn àjọyọ̀ àtìgbàdégbà+ tó jẹ́ ti Jèhófà tí ẹ máa kéde pé wọ́n jẹ́ àpéjọ mímọ́,+ láti máa fi mú ọrẹ àfinásun wá fún Jèhófà: ẹbọ sísun+ àti ọrẹ ọkà+ tó jẹ́ ti ẹbọ àti àwọn ọrẹ ohun mímu+ gẹ́gẹ́ bí ètò ojoojúmọ́. 38 Nǹkan wọ̀nyí jẹ́ àfikún sí ohun tí ẹ fi rúbọ ní àwọn sábáàtì Jèhófà+ àti àwọn ẹ̀bùn yín,+ àwọn ọrẹ tí ẹ jẹ́jẹ̀ẹ́+ àti àwọn ọrẹ àtinúwá yín,+ tí ẹ máa fún Jèhófà. 39 Ní ọjọ́ kẹẹ̀ẹ́dógún oṣù keje, tí ẹ bá ti kórè èso ilẹ̀ náà, kí ẹ fi ọjọ́ méje+ ṣe àjọyọ̀ fún Jèhófà. Ní ọjọ́ kìíní, kí ẹ sinmi, kí ẹ má ṣiṣẹ́ rárá. Ní ọjọ́ kẹjọ pẹ̀lú, kí ẹ sinmi, kí ẹ má ṣiṣẹ́ rárá.+ 40 Ní ọjọ́ kìíní, kí ẹ mú èso àwọn igi ńláńlá, àwọn imọ̀ ọ̀pẹ,+ àwọn ẹ̀ka igi eléwé púpọ̀ àti àwọn igi pọ́pílà tó wà ní àfonífojì, kí ẹ sì yọ̀+ níwájú Jèhófà Ọlọ́run yín fún ọjọ́ méje.+ 41 Ọjọ́ méje ni kí ẹ máa fi ṣe àjọyọ̀ náà fún Jèhófà lọ́dọọdún.+ Àṣẹ tí gbogbo ìran yín á máa pa mọ́ títí lọ ni. Oṣù keje ni kí ẹ máa ṣe é. 42 Inú àtíbàbà ni kí ẹ gbé fún ọjọ́ méje.+ Kí gbogbo àwọn ọmọ ìbílẹ̀ Ísírẹ́lì gbé inú àtíbàbà, 43 kí àwọn ìran yín tó ń bọ̀ lè mọ̀+ pé inú àtíbàbà ni mo mú kí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì gbé nígbà tí mo mú wọn kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì.+ Èmi ni Jèhófà Ọlọ́run yín.’”
44 Mósè sì sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nípa àwọn àjọyọ̀ àtìgbàdégbà ti Jèhófà.
24 Jèhófà ń bá ọ̀rọ̀ tó ń sọ fún Mósè lọ pé: 2 “Pàṣẹ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé kí wọ́n gbé ògidì òróró ólífì tí wọ́n fún wá sọ́dọ̀ rẹ láti máa fi tan iná, kí àwọn fìtílà náà lè máa wà ní títàn nígbà gbogbo.+ 3 Lẹ́yìn òde aṣọ ìdábùú Ẹ̀rí nínú àgọ́ ìpàdé, kí Áárónì ṣètò bí àwọn fìtílà náà á ṣe máa wà ní títàn níwájú Jèhófà nígbà gbogbo láti ìrọ̀lẹ́ di òwúrọ̀. Àṣẹ tí gbogbo ìran yín á máa tẹ̀ lé títí láé ni. 4 Kó máa to àwọn fìtílà náà sórí ọ̀pá fìtílà+ tí wọ́n fi ògidì wúrà ṣe, èyí tó wà níwájú Jèhófà nígbà gbogbo.
5 “Kí o mú ìyẹ̀fun tó kúnná, kí o fi ṣe búrẹ́dì méjìlá (12) tó rí bí òrùka. Ìyẹ̀fun tó jẹ́ ìdá méjì nínú mẹ́wàá òṣùwọ̀n eéfà* ni kí o fi ṣe búrẹ́dì kọ̀ọ̀kan. 6 Kí o tò wọ́n ní ìpele méjì, mẹ́fà ní ìpele kan,+ lórí tábìlì tí wọ́n fi ògidì wúrà ṣe, èyí tó wà níwájú Jèhófà.+ 7 Kí o fi ògidì oje igi tùràrí sórí ìpele kọ̀ọ̀kan, yóò sì jẹ́ búrẹ́dì ọrẹ ìṣàpẹẹrẹ*+ tó jẹ́ ọrẹ àfinásun sí Jèhófà. 8 Kó máa tò ó síwájú Jèhófà nígbà gbogbo+ ní ọjọ́ Sábáàtì kọ̀ọ̀kan. Májẹ̀mú tí mo bá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì dá ni, ó sì máa wà títí lọ. 9 Yóò di ti Áárónì àti àwọn ọmọ rẹ̀,+ wọ́n á sì jẹ ẹ́ ní ibi mímọ́,+ torí ó jẹ́ ohun mímọ́ jù lọ fún un látinú àwọn ọrẹ àfinásun sí Jèhófà, ìlànà tó máa wà títí lọ ni.”
10 Ó ṣẹlẹ̀ pé, láàárín àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, ọmọkùnrin kan wà tí ìyá rẹ̀ jẹ́ ọmọ Ísírẹ́lì, tí bàbá rẹ̀ sì jẹ́ ará Íjíbítì.+ Òun àti ọkùnrin kan tó jẹ́ ọmọ Ísírẹ́lì wá ń bá ara wọn jà nínú ibùdó. 11 Ọmọkùnrin tí ìyá rẹ̀ jẹ́ ọmọ Ísírẹ́lì náà wá bẹ̀rẹ̀ sí í tàbùkù sí Orúkọ náà,* ó sì ń sọ̀rọ̀ òdì sí i.*+ Torí náà, wọ́n mú un wá sọ́dọ̀ Mósè.+ Ó ṣẹlẹ̀ pé, Ṣẹ́lómítì ni orúkọ ìyá rẹ̀, ọmọ Díbírì látinú ẹ̀yà Dánì. 12 Wọ́n fi ọmọkùnrin náà sínú àhámọ́ títí ìpinnu Jèhófà fi ṣe kedere sí wọn.+
13 Jèhófà wá sọ fún Mósè pé: 14 “Mú ẹni tó ṣépè náà wá sí ẹ̀yìn ibùdó, kí gbogbo àwọn tó gbọ́ ohun tó sọ gbé ọwọ́ wọn lé e lórí, kí gbogbo àpéjọ náà sì sọ ọ́ lókùúta.+ 15 Kí o sì sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé, ‘Tí ẹnikẹ́ni bá sọ̀rọ̀ òdì sí Ọlọ́run rẹ̀, yóò jìyà ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀. 16 Torí náà, ẹ gbọ́dọ̀ pa ẹni tó bá tàbùkù sí orúkọ Jèhófà.+ Gbogbo àpéjọ náà gbọ́dọ̀ sọ ọ́ lókùúta. Ì báà jẹ́ àjèjì tàbí ọmọ ìbílẹ̀ ló tàbùkù sí Orúkọ náà, ṣe ni kí ẹ pa á.
17 “‘Tí ẹnì kan bá gbẹ̀mí èèyàn,* ẹ gbọ́dọ̀ pa á.+ 18 Tí ẹnikẹ́ni bá lu ẹran ọ̀sìn pa,* kó san ohun kan dípò, ẹ̀mí dípò ẹ̀mí. 19 Tí ẹnì kan bá ṣe ẹnì kejì rẹ̀ léṣe, ohun tó ṣe ni kí ẹ ṣe fún òun náà.+ 20 Kí ẹ kán eegun ẹni tó bá kán eegun ẹlòmíì, ojú dípò ojú, eyín dípò eyín, ohun tó bá ṣe fún ẹlòmíì ni kí ẹ ṣe fún òun náà.+ 21 Tí ẹnì kan bá lu ẹran pa, kó san ohun kan dípò,+ àmọ́ ṣe ni kí ẹ pa ẹni tó bá lu èèyàn pa.+
22 “‘Ìdájọ́ kan náà ni kí ẹ máa tẹ̀ lé, ì báà jẹ́ àjèjì tàbí ọmọ ìbílẹ̀,+ torí èmi ni Jèhófà Ọlọ́run yín.’”
23 Lẹ́yìn náà, Mósè bá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sọ̀rọ̀, wọ́n mú ẹni tó sọ̀rọ̀ òdì náà wá sí ẹ̀yìn ibùdó, wọ́n sì sọ ọ́ lókùúta.+ Nípa bẹ́ẹ̀, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe ohun tí Jèhófà pa láṣẹ fún Mósè gẹ́lẹ́.
25 Jèhófà tún sọ fún Mósè lórí Òkè Sínáì pé: 2 “Sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé, ‘Tí ẹ bá dé ilẹ̀ tí màá fún yín,+ kí ilẹ̀ náà pa sábáàtì mọ́ fún Jèhófà.+ 3 Ọdún mẹ́fà ni kí ẹ fi fún irúgbìn sí oko yín, ọdún mẹ́fà ni kí ẹ fi rẹ́wọ́ ọgbà àjàrà yín, kí ẹ sì kórè èso ilẹ̀ náà.+ 4 Àmọ́ kí ọdún keje jẹ́ sábáàtì fún ilẹ̀ náà, tí ẹ ò ní ṣiṣẹ́ kankan níbẹ̀, sábáàtì fún Jèhófà. Ẹ ò gbọ́dọ̀ fún irúgbìn sí oko yín tàbí kí ẹ rẹ́wọ́ àjàrà yín. 5 Ẹ ò gbọ́dọ̀ kórè ohun tó hù fúnra rẹ̀ látinú ọkà tó ṣẹ́ kù lẹ́yìn tí ẹ kórè, ẹ má sì kó àwọn èso àjàrà yín tí ẹ ò tíì rẹ́wọ́ rẹ̀ jọ. Ẹ jẹ́ kí ilẹ̀ náà sinmi pátápátá fún ọdún kan. 6 Àmọ́ ẹ lè jẹ ohun tó bá hù ní ilẹ̀ náà nígbà sábáàtì rẹ̀; ẹ̀yin, ẹrúkùnrin àti ẹrúbìnrin yín, àwọn alágbàṣe yín àti àwọn àjèjì tó ń gbé láàárín yín lè jẹ ẹ́, 7 títí kan àwọn ẹran ọ̀sìn àti ẹran inú igbó tó wà ní ilẹ̀ yín. Ẹ lè jẹ gbogbo ohun tó bá so ní ilẹ̀ náà.
8 “‘Kí o ka ọdún sábáàtì méje, ọdún méje ní ìlọ́po méje, iye ọdún sábáàtì méje náà yóò sì jẹ́ ọdún mọ́kàndínláàádọ́ta (49). 9 Kí o wá fun ìwo kíkankíkan ní ọjọ́ kẹwàá oṣù keje; ní Ọjọ́ Ètùtù,+ kí o mú kí ìró ìwo náà dún ní gbogbo ilẹ̀ yín. 10 Kí ẹ ya ọdún àádọ́ta (50) sí mímọ́, kí ẹ sì kéde òmìnira fún gbogbo àwọn tó ń gbé ilẹ̀ náà.+ Yóò di Júbílì fún yín, kálukú yín á pa dà sídìí ohun ìní rẹ̀, kálukú yín á sì pa dà sọ́dọ̀ ìdílé rẹ̀.+ 11 Júbílì ni ọdún àádọ́ta (50) náà yóò jẹ́ fún yín. Ẹ ò gbọ́dọ̀ fún irúgbìn tàbí kí ẹ kórè ohun tó hù fúnra rẹ̀ látinú ọkà tó ṣẹ́ kù tàbí kí ẹ kórè èso àjàrà tí ẹ ò tíì rẹ́wọ́ rẹ̀.+ 12 Torí Júbílì ni. Kó di mímọ́ fún yín. Ohun tí ilẹ̀ náà bá mú jáde nìkan ni kí ẹ máa jẹ.+
13 “‘Ní ọdún Júbílì yìí, kí kálukú yín pa dà sídìí ohun ìní rẹ̀.+ 14 Tí ẹ bá ta ohunkóhun fún ọmọnìkejì yín tàbí tí ẹ ra ohunkóhun lọ́wọ́ rẹ̀, ẹ má ṣe rẹ́ ara yín jẹ.+ 15 Ọwọ́ ọmọnìkejì rẹ ni kí o ti rà á, wo iye ọdún tó tẹ̀ lé Júbílì, iye ọdún tó bá sì kù láti kórè ni kó fi tà á fún ọ.+ 16 Tí iye ọdún tó ṣẹ́ kù bá pọ̀, ó lè fowó lé iye tó fẹ́ tà á, àmọ́ tí iye ọdún tó kù kò bá pọ̀, kó dín iye tó fẹ́ tà á kù, torí iye irè oko tó máa hù ló fẹ́ tà fún ọ. 17 Ẹnì kankan nínú yín ò gbọ́dọ̀ rẹ́ ọmọnìkejì rẹ̀ jẹ,+ ẹ sì gbọ́dọ̀ bẹ̀rù Ọlọ́run yín,+ torí èmi ni Jèhófà Ọlọ́run yín.+ 18 Tí ẹ bá ń pa àwọn àṣẹ mi mọ́, tí ẹ sì ń tẹ̀ lé àwọn ìdájọ́ mi, ẹ máa gbé ilẹ̀ náà láìséwu.+ 19 Ilẹ̀ náà yóò mú èso jáde,+ ẹ ó jẹ àjẹyó, ẹ ó sì máa gbé láìséwu+ níbẹ̀.
20 “‘Àmọ́ tí ẹ bá sọ pé: “Kí la máa jẹ ní ọdún keje tí a ò bá fún irúgbìn, tí a ò sì kórè?”+ 21 Màá bù kún yín ní ọdún kẹfà, ilẹ̀ náà yóò sì so èso tó máa tó fún ọdún mẹ́ta.+ 22 Kí ẹ wá fún irúgbìn ní ọdún kẹjọ, kí ẹ máa jẹ látinú irè oko tó ti wà nílẹ̀ títí di ọdún kẹsàn-án. Títí ilẹ̀ náà yóò fi mú èso jáde, kí ẹ máa jẹ èyí tó ti wà nílẹ̀.
23 “‘Ẹ ò gbọ́dọ̀ ta ilẹ̀ náà títí láé,+ torí tèmi ni ilẹ̀ náà.+ Ojú àjèjì àti àlejò ni mo fi ń wò yín.+ 24 Kí ẹ jẹ́ kí ẹ̀tọ́ láti ra ilẹ̀ pa dà wà ní gbogbo ilẹ̀ tó jẹ́ tiyín.
25 “‘Tí arákùnrin rẹ bá di aláìní, tó sì tà lára ohun ìní rẹ̀, kí olùtúnrà tó bá a tan tímọ́tímọ́ wá ra ohun tí arákùnrin rẹ̀ tà pa dà.+ 26 Tí ẹnì kan ò bá ní olùtúnrà, àmọ́ tó ti wá lọ́rọ̀, tó sì lágbára láti tún ohun ìní náà rà, 27 kó ṣírò iye rẹ̀ láti ọdún tó ti tà á, kó sì dá owó tó ṣẹ́ kù pa dà fún ẹni tó tà á fún. Ohun ìní rẹ̀ á wá pa dà di tirẹ̀.+
28 “‘Àmọ́ tí kò bá lágbára láti gbà á pa dà lọ́wọ́ ẹni náà, ohun tó tà máa wà lọ́wọ́ ẹni tó rà á títí di ọdún Júbílì;+ yóò pa dà sọ́wọ́ rẹ̀ nígbà Júbílì, ohun ìní rẹ̀ á sì pa dà di tirẹ̀.+
29 “‘Tí ọkùnrin kan bá ta ilé kan nínú ìlú olódi, kí ẹ̀tọ́ tó ní láti ṣe àtúnrà ṣì wà láti ìgbà tó bá ti tà á títí ọdún yóò fi parí; ó ní ẹ̀tọ́ láti ṣe àtúnrà+ láàárín ọdún kan gbáko. 30 Àmọ́ tí kò bá rà á pa dà títí ọdún kan fi pé, kí ilé tó wà nínú ìlú olódi náà di ohun ìní ẹni tó rà á títí láé jálẹ̀ àwọn ìran rẹ̀. Kò gbọ́dọ̀ dá a pa dà nígbà Júbílì. 31 Àmọ́ kí ẹ ka àwọn ilé gbígbé tí kò sí ògiri tó yí i ká sí ara ilẹ̀ ìgbèríko. Kí ẹ̀tọ́ láti ṣe àtúnrà rẹ̀ ṣì wà, kó sì pa dà di tàwọn tó ni ín nígbà Júbílì.
32 “‘Ní ti ilé àwọn ọmọ Léfì tó wà nínú àwọn ìlú wọn,+ àwọn ọmọ Léfì máa ní ẹ̀tọ́ láti ṣe àtúnrà àwọn ilé náà títí láé. 33 Tí àwọn ọmọ Léfì ò bá ra ohun ìní wọn pa dà, kí ilé tí wọ́n tà nínú ìlú wọn pa dà di tiwọn nígbà Júbílì,+ torí àwọn ilé tó wà nínú àwọn ìlú àwọn ọmọ Léfì jẹ́ ohun ìní wọn láàárín àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.+ 34 Bákan náà, ẹ má ta ibi ìjẹko+ tó yí àwọn ìlú wọn ká, torí ohun ìní wọn ló jẹ́ títí láé.
35 “‘Tí arákùnrin rẹ tó wà nítòsí bá di aláìní, tí kò sì lè bójú tó ara rẹ̀, kí o ràn án lọ́wọ́+ bí o ṣe máa ṣe fún àjèjì àti àlejò,+ kó lè máa wà láàyè pẹ̀lú rẹ. 36 Má gba èlé tàbí kí o jèrè lára rẹ̀.*+ Kí o máa bẹ̀rù Ọlọ́run rẹ,+ arákùnrin rẹ yóò sì máa wà láàyè pẹ̀lú rẹ. 37 Má ṣe yá a lówó èlé+ tàbí kí o gba èrè lórí oúnjẹ rẹ tí o fún un. 38 Èmi ni Jèhófà Ọlọ́run yín, tó mú yín kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì+ láti fún yín ní ilẹ̀ Kénáánì, láti jẹ́ kí ẹ mọ̀ pé èmi ni Ọlọ́run yín.+
39 “‘Tí arákùnrin rẹ tó ń gbé nítòsí bá di aláìní, tó sì ní láti ta ara rẹ̀ fún ọ,+ má fipá mú un ṣe ẹrú.+ 40 Bí alágbàṣe,+ bí àlejò ni kí o ṣe mú un. Kó máa sìn ọ́ títí di ọdún Júbílì. 41 Kó sì kúrò lọ́dọ̀ rẹ, òun àti àwọn ọmọ* rẹ̀, kó pa dà sọ́dọ̀ ìdílé rẹ̀. Kó pa dà sídìí ohun ìní àwọn baba ńlá rẹ̀.+ 42 Torí ẹrú mi tí mo mú kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì ni wọ́n.+ Kí wọ́n má ta ara wọn bí ẹni ta ẹrú. 43 Má hùwà ìkà sí i,+ kí o sì máa bẹ̀rù Ọlọ́run rẹ.+ 44 Inú àwọn orílẹ̀-èdè tó yí yín ká ni kí ẹrúkùnrin àti ẹrúbìnrin yín ti wá, ẹ lè ra ẹrúkùnrin àti ẹrúbìnrin lọ́wọ́ wọn. 45 Bákan náà, ẹ lè ra ẹrú lọ́wọ́ àwọn ọmọ àjèjì tó ń bá yín gbé+ àti lọ́wọ́ ìdílé wọn, àwọn tí wọ́n bí fún wọn ní ilẹ̀ yín, wọ́n á sì di tiyín. 46 Ẹ lè jẹ́ kí àwọn ọmọ yín jogún wọn kí wọ́n lè di ohun ìní wọn títí láé. Ẹ lè lò wọ́n bí òṣìṣẹ́, àmọ́ ẹ má fi ọwọ́ líle mú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó jẹ́ arákùnrin yín.+
47 “‘Àmọ́ tí àjèjì tàbí àlejò kan láàárín yín bá di ọlọ́rọ̀, tí arákùnrin rẹ tó wà nítòsí rẹ̀ di aláìní, tó sì ní láti ta ara rẹ̀ fún àjèjì tàbí àlejò náà tó ń gbé láàárín yín tàbí ọ̀kan lára mọ̀lẹ́bí àjèjì náà, 48 ó ṣì máa ní ẹ̀tọ́ láti ṣe àtúnrà lẹ́yìn tó ta ara rẹ̀. Ọ̀kan nínú àwọn arákùnrin rẹ̀ lè rà á pa dà+ 49 tàbí kí arákùnrin òbí rẹ̀ tàbí ọmọkùnrin tí arákùnrin òbí rẹ̀ bí rà á pa dà. Èyíkéyìí nínú àwọn mọ̀lẹ́bí rẹ̀ tó sún mọ́ ọn,* tó jẹ́ ara ìdílé rẹ̀ lè rà á pa dà.
“‘Tí òun fúnra rẹ̀ bá sì ti di ọlọ́rọ̀, ó lè ra ara rẹ̀ pa dà.+ 50 Kí òun àti ẹni tó rà á ṣírò iye ọdún tó jẹ́ láti ọdún tó ti ta ara rẹ̀ fún un títí di ọdún Júbílì,+ kí owó tó sì ta ara rẹ̀ ṣe rẹ́gí pẹ̀lú iye ọdún náà.+ Bí wọ́n ṣe ń ṣírò owó alágbàṣe+ ni wọ́n á ṣe ṣírò owó rẹ̀ láwọn ọjọ́ tó fi ṣiṣẹ́ ní àkókò yẹn. 51 Tí ọdún tó kù bá ṣì pọ̀, kó san iye owó ìtúnrà rẹ̀ ní ìbámu pẹ̀lú iye ọdún tó kù. 52 Àmọ́ tí ọdún tó kù kí ọdún Júbílì tó dé kò bá pọ̀, kó ṣírò rẹ̀, kó sì san owó ìtúnrà ní ìbámu pẹ̀lú iye ọdún tó kù. 53 Kó máa sìn ín bí alágbàṣe lọ́dọọdún; kí o sì rí i pé kò fọwọ́ líle mú un.+ 54 Àmọ́ tí kò bá lè ra ara rẹ̀ pa dà bí mo ṣe là á kalẹ̀ yìí, kó máa lọ lómìnira nígbà ọdún Júbílì,+ òun àti àwọn ọmọ* rẹ̀.
55 “‘Torí ẹrú mi ni àwọn ọmọ Ísírẹ́lì. Àwọn ni ẹrú mi tí mo mú kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì.+ Èmi ni Jèhófà Ọlọ́run yín.
26 “‘Ẹ ò gbọ́dọ̀ ṣe àwọn ọlọ́run tí kò ní láárí fún ara yín,+ ẹ ò gbọ́dọ̀ ṣe ère gbígbẹ́+ tàbí ọwọ̀n òrìṣà fún ara yín, ẹ ò sì gbọ́dọ̀ gbé ère òkúta+ tí ẹ gbẹ́ sí ilẹ̀ yín láti forí balẹ̀ fún un;+ torí èmi ni Jèhófà Ọlọ́run yín. 2 Kí ẹ máa pa àwọn sábáàtì mi mọ́, kí ẹ sì máa bọ̀wọ̀ fún* ibi mímọ́ mi. Èmi ni Jèhófà.
3 “‘Tí ẹ bá ń tẹ̀ lé àwọn òfin mi, tí ẹ̀ ń pa àwọn àṣẹ mi mọ́, tí ẹ sì ń ṣe wọ́n,+ 4 èmi yóò rọ ọ̀wààrà òjò fún yín ní àkókò tó yẹ,+ ilẹ̀ yóò mú èso jáde,+ àwọn igi oko yóò sì so èso. 5 Ẹ ó máa pakà títí di ìgbà tí ẹ máa kórè èso àjàrà, ẹ ó sì máa kórè èso àjàrà títí di ìgbà tí ẹ máa fúnrúgbìn; ẹ ó jẹun ní àjẹyó, ẹ ó sì máa gbé láìséwu ní ilẹ̀ yín.+ 6 Màá mú kí àlàáfíà wà ní ilẹ̀ náà,+ ẹ ó sì dùbúlẹ̀ láìsí ẹni tó máa dẹ́rù bà yín;+ màá mú àwọn ẹranko burúkú kúrò ní ilẹ̀ náà, idà ogun ò sì ní kọjá ní ilẹ̀ yín. 7 Ó dájú pé ẹ máa lé àwọn ọ̀tá yín, ẹ ó sì fi idà ṣẹ́gun wọn. 8 Ẹ̀yin márùn-ún yóò lé ọgọ́rùn-ún (100), ẹ̀yin ọgọ́rùn-ún (100) yóò lé ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá (10,000), ẹ ó sì fi idà ṣẹ́gun àwọn ọ̀tá yín.+
9 “‘Màá ṣojúure* sí yín, màá mú kí ẹ bímọ lémọ, kí ẹ sì di púpọ̀,+ màá sì mú májẹ̀mú tí mo bá yín dá ṣẹ.+ 10 Bí ẹ ṣe ń jẹ irè oko tó ṣẹ́ kù láti ọdún tó kọjá, ẹ máa ní láti palẹ̀ èyí tó ṣẹ́ kù mọ́ kí tuntun lè wọlé. 11 Màá gbé àgọ́ ìjọsìn mi sáàárín yín,+ mi* ò sì ní kọ̀ yín. 12 Èmi yóò máa rìn láàárín yín, èmi yóò sì jẹ́ Ọlọ́run yín,+ ẹ̀yin ní tiyín, yóò sì jẹ́ èèyàn mi.+ 13 Èmi ni Jèhófà Ọlọ́run yín, tó mú yín kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì, kí ẹ má bàa ṣe ẹrú wọn mọ́. Mo ṣẹ́ àwọn ọ̀pá àjàgà yín, mo sì mú kí ẹ lè nàró ṣánṣán bí ẹ ṣe ń rìn.*
14 “‘Àmọ́, tí ẹ ò bá fetí sí mi, tí ẹ ò sì pa gbogbo àṣẹ yìí mọ́,+ 15 tí ẹ bá kọ àwọn òfin mi,+ tí ẹ* sì kórìíra àwọn ìdájọ́ mi débi pé ẹ ò pa gbogbo àṣẹ mi mọ́, tí ẹ sì da májẹ̀mú mi,+ 16 èmi, ní tèmi, yóò ṣe nǹkan wọ̀nyí sí yín: màá kó ìdààmú bá yín láti fìyà jẹ yín, màá fi ikọ́ ẹ̀gbẹ àti akọ ibà ṣe yín, yóò mú kí ojú yín di bàìbàì, kí ẹ* sì ṣègbé. Lásán ni ẹ máa fún irúgbìn yín, torí àwọn ọ̀tá yín ni yóò jẹ ẹ́.+ 17 Mi ò ní fojúure wò yín, àwọn ọ̀tá yín á sì ṣẹ́gun yín;+ àwọn tó kórìíra yín yóò tẹ̀ yín mọ́lẹ̀,+ ẹ ó sì sá nígbà tí ẹnì kankan ò lé yín.+
18 “‘Tí ẹ ò bá wá fetí sí mi lẹ́yìn èyí, ṣe ni màá fi ìyà ẹ̀ṣẹ̀ yín jẹ yín ní ìlọ́po méje. 19 Màá fòpin sí ìgbéraga yín, màá mú kí ojú ọ̀run yín dà bí irin+ àti ilẹ̀ yín bíi bàbà. 20 Lásán ni ẹ máa lo gbogbo agbára yín, torí ilẹ̀ yín kò ní mú èso rẹ̀ jáde,+ àwọn igi ilẹ̀ yín kò sì ní so èso.
21 “‘Tí ẹ bá ṣì ń kẹ̀yìn sí mi, tí ẹ ò sì fetí sí mi, ṣe ni màá fi ìyà ẹ̀ṣẹ̀ yín jẹ yín ní ìlọ́po méje. 22 Èmi yóò rán àwọn ẹran inú igbó sáàárín yín,+ wọ́n á pa yín lọ́mọ jẹ,+ wọ́n á pa àwọn ẹran ọ̀sìn yín run, wọ́n á dín iye yín kù, àwọn ọ̀nà yín yóò sì dá páropáro.+
23 “‘Lẹ́yìn nǹkan wọ̀nyí, tí ẹ kò bá gba ìbáwí tí mo fún yín,+ tí ẹ ṣì ń kẹ̀yìn sí mi, 24 èmi náà yóò kẹ̀yìn sí yín, èmi fúnra mi yóò sì fìyà jẹ yín ní ìlọ́po méje torí ẹ̀ṣẹ̀ yín. 25 Èmi yóò mú idà ẹ̀san wá sórí yín torí ẹ da májẹ̀mú+ náà. Tí ẹ bá kóra jọ sínú àwọn ìlú yín, èmi yóò rán àrùn sí àárín yín,+ màá sì mú kí ọwọ́ àwọn ọ̀tá yín tẹ̀ yín.+ 26 Tí mo bá run ibi* tí ẹ kó búrẹ́dì*+ yín jọ sí, obìnrin mẹ́wàá ni yóò yan búrẹ́dì yín nínú ààrò kan ṣoṣo, wọ́n á máa wọn búrẹ́dì fún yín;+ ẹ ó jẹ, àmọ́ ẹ ò ní yó.+
27 “‘Lẹ́yìn nǹkan wọ̀nyí, tí ẹ ò bá fetí sí mi, tí ẹ ṣì ń kẹ̀yìn sí mi, 28 èmi yóò túbọ̀ kẹ̀yìn sí yín,+ èmi fúnra mi yóò sì fi ìyà ẹ̀ṣẹ̀ yín jẹ yín ní ìlọ́po méje. 29 Torí náà, ṣe ni ẹ máa jẹ ẹran ara àwọn ọmọkùnrin yín, ẹ ó sì jẹ ẹran ara àwọn ọmọbìnrin yín.+ 30 Èmi yóò run àwọn ibi gíga+ tí ẹ ti ń sin àwọn òrìṣà yín, màá wó àwọn pẹpẹ tùràrí yín lulẹ̀, màá sì to òkú yín jọ pelemọ sórí òkú àwọn òrìṣà ẹ̀gbin*+ yín, èmi* yóò pa yín tì, màá sì kórìíra yín.+ 31 Èmi yóò mú kí idà pa àwọn ìlú yín,+ màá sì sọ àwọn ibi mímọ́ yín di ahoro, mi ò ní gbọ́ òórùn dídùn* àwọn ẹbọ yín. 32 Èmi fúnra mi yóò mú kí ilẹ̀ náà di ahoro,+ àwọn ọ̀tá yín tó ń gbé ibẹ̀ yóò sì máa wò ó tìyanutìyanu.+ 33 Èmi yóò tú yín ká sáàárín àwọn orílẹ̀-èdè,+ màá sì fa idà yọ látinú àkọ̀ láti lé yín bá;+ ilẹ̀ yín yóò di ahoro,+ àwọn ìlú yín yóò sì pa run.
34 “‘Nígbà yẹn, ilẹ̀ náà yóò san àwọn sábáàtì rẹ̀ ní gbogbo ọjọ́ tó bá fi wà ní ahoro, nígbà tí ẹ bá wà ní ilẹ̀ àwọn ọ̀tá yín. Nígbà yẹn, ilẹ̀ náà máa sinmi,* torí ó gbọ́dọ̀ san àwọn sábáàtì rẹ̀ pa dà.+ 35 Yóò sinmi ní gbogbo ọjọ́ tó bá fi wà ní ahoro, torí kò sinmi nígbà àwọn sábáàtì yín, nígbà tí ẹ̀ ń gbé ibẹ̀.
36 “‘Ní ti àwọn tó bá yè é,+ màá fi ìbẹ̀rù kún ọkàn wọn ní ilẹ̀ àwọn ọ̀tá wọn; ìró ewé tí atẹ́gùn ń fẹ́ máa lé wọn sá, wọ́n á fẹsẹ̀ fẹ bí ẹni ń sá fún idà, wọ́n á sì ṣubú láìsí ẹni tó ń lé wọn.+ 37 Wọ́n á kọ lu ara wọn bí ẹni ń sá fún idà, bó tiẹ̀ jẹ́ pé kò sẹ́ni tó ń lé wọn. Ẹ ò ní lè kojú àwọn ọ̀tá yín.+ 38 Ẹ ó ṣègbé láàárín àwọn orílẹ̀-èdè,+ ilẹ̀ àwọn ọ̀tá yín yóò sì jẹ yín run. 39 Àwọn tó bá ṣẹ́ kù nínú yín máa jẹrà sí ilẹ̀ àwọn ọ̀tá yín+ torí ẹ̀ṣẹ̀ yín. Àní, wọn yóò jẹrà dà nù torí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn bàbá wọn.+ 40 Wọ́n á wá jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ ara wọn+ àti ẹ̀ṣẹ̀ àwọn bàbá wọn pẹ̀lú ìwà àìṣòótọ́ àwọn bàbá wọn, wọ́n á sì gbà pé àwọn ti hùwà àìṣòótọ́ torí wọ́n kẹ̀yìn sí mi.+ 41 Èmi náà sì kẹ̀yìn sí wọn,+ torí mo mú wọn wá sí ilẹ̀ àwọn ọ̀tá wọn.+
“‘Bóyá nígbà yẹn, wọ́n á rẹ ọkàn wọn tí wọn ò kọ nílà* wálẹ̀,+ wọ́n á sì wá jìyà ẹ̀ṣẹ̀ wọn. 42 Màá sì rántí májẹ̀mú tí mo bá Jékọ́bù dá+ àti májẹ̀mú tí mo bá Ísákì dá,+ màá rántí májẹ̀mú tí mo bá Ábúráhámù dá,+ màá sì rántí ilẹ̀ náà. 43 Nígbà tí wọ́n pa ilẹ̀ náà tì, ó ń san àwọn sábáàtì rẹ̀,+ ó wà ní ahoro nígbà tí wọn ò sí níbẹ̀, wọ́n sì ń jìyà ẹ̀ṣẹ̀ wọn, torí wọ́n kọ àwọn ìdájọ́ mi, wọ́n* sì kórìíra àwọn àṣẹ mi.+ 44 Àmọ́ láìka gbogbo èyí sí, nígbà tí wọ́n ṣì wà ní ilẹ̀ àwọn ọ̀tá wọn, mi ò ní kọ̀ wọ́n pátápátá+ tàbí kí n ta wọ́n nù débi pé màá pa wọ́n run pátápátá, torí ìyẹn á da májẹ̀mú tí mo bá wọn dá,+ torí èmi ni Jèhófà Ọlọ́run wọn. 45 Nítorí wọn, màá rántí májẹ̀mú tí mo bá àwọn baba ńlá wọn dá,+ àwọn tí mo mú kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì níṣojú àwọn orílẹ̀-èdè,+ láti fi hàn pé èmi ni Ọlọ́run wọn. Èmi ni Jèhófà.’”
46 Èyí ni àwọn ìlànà, àwọn ìdájọ́ àti àwọn òfin tí Jèhófà gbé kalẹ̀ láàárín òun àti àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lórí Òkè Sínáì nípasẹ̀ Mósè.+
27 Jèhófà ń bá ọ̀rọ̀ tó ń sọ fún Mósè lọ pé: 2 “Sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé, ‘Tí ẹnì kan bá jẹ́ ẹ̀jẹ́ pàtàkì+ láti mú iye tí wọ́n dá lé ẹnì* kan wá fún Jèhófà, 3 kí iye tí wọ́n máa dá lé ọkùnrin tó jẹ́ ẹni ogún (20) ọdún sí ọgọ́ta (60) ọdún jẹ́ àádọ́ta (50) ṣékélì* fàdákà, kó jẹ́ ìwọ̀n ṣékélì ibi mímọ́.* 4 Àmọ́ tó bá jẹ́ obìnrin, kí iye tí wọ́n máa dá lé e jẹ́ ọgbọ̀n (30) ṣékélì. 5 Tí ẹni náà bá jẹ́ ẹni ọdún márùn-ún sí ogún (20) ọdún, kí iye tí wọ́n máa dá lé ọkùnrin jẹ́ ogún (20) ṣékélì, kí ti obìnrin sì jẹ́ ṣékélì mẹ́wàá. 6 Tó bá jẹ́ ọmọ oṣù kan sí ọdún márùn-ún, kí iye tí wọ́n máa dá lé ọkùnrin jẹ́ ṣékélì fàdákà márùn-ún, kí ti obìnrin sì jẹ́ ṣékélì fàdákà mẹ́ta.
7 “‘Tó bá jẹ́ ẹni ọgọ́ta (60) ọdún sókè, kí iye tí wọ́n máa dá lé ọkùnrin jẹ́ ṣékélì mẹ́ẹ̀ẹ́dógún (15), kí ti obìnrin sì jẹ́ ṣékélì mẹ́wàá. 8 Àmọ́ tí ẹni náà bá tòṣì débi pé kò lè san owó náà,+ kó dúró níwájú àlùfáà, kí àlùfáà sì díye lé e. Kí iye tí àlùfáà máa dá lé e jẹ́ iye tí agbára ẹni tó jẹ́jẹ̀ẹ́ náà máa ká.+
9 “‘Tó bá jẹ́ ẹran tó bójú mu láti fi ṣe ọrẹ fún Jèhófà ló jẹ́jẹ̀ẹ́ pé òun máa mú wá, ohunkóhun tó bá fún Jèhófà yóò di mímọ́. 10 Kó má pààrọ̀ rẹ̀, kó má sì fi èyí tó dáa rọ́pò èyí tí kò dáa tàbí kó fi èyí tí kò dáa rọ́pò èyí tó dáa. Àmọ́ tó bá fi ẹran pààrọ̀ ẹran, ẹran tó pààrọ̀ àti èyí tó fi pààrọ̀ yóò di ohun mímọ́. 11 Tó bá jẹ́ ẹran aláìmọ́,+ tí kò bójú mu ló mú wá láti fi ṣe ọrẹ fún Jèhófà, kó mú kí ẹran náà dúró níwájú àlùfáà. 12 Kí àlùfáà wá díye lé e, bó bá ṣe dáa tàbí bó ṣe burú sí. Iye tí àlùfáà bá dá lé e ni yóò jẹ́. 13 Àmọ́ tó bá tiẹ̀ fẹ́ rà á pa dà, ó gbọ́dọ̀ fi ìdá márùn-ún iye tí wọ́n dá lé e kún un.+
14 “‘Tí ẹnì kan bá ya ilé rẹ̀ sí mímọ́, tó fi ṣe ohun mímọ́ fún Jèhófà, kí àlùfáà díye lé e, bó bá ṣe dáa tàbí bó ṣe burú sí. Iye tí àlùfáà bá dá lé e ni iye owó rẹ̀ yóò jẹ́.+ 15 Àmọ́ tí ẹni tó ya ilé náà sí mímọ́ bá fẹ́ rà á pa dà, ó gbọ́dọ̀ fi ìdá márùn-ún iye tí wọ́n dá lé e kún un, yóò sì di tirẹ̀.
16 “‘Tí ẹnì kan bá ya apá kan lára ilẹ̀ rẹ̀ sí mímọ́ fún Jèhófà, iye irúgbìn tí wọ́n máa fún sínú rẹ̀ ni wọ́n á fi díwọ̀n iye tí wọ́n máa dá lé e: ọkà bálì tó kún òṣùwọ̀n hómérì* kan máa jẹ́ àádọ́ta (50) ṣékélì fàdákà. 17 Tó bá ya ilẹ̀ rẹ̀ sí mímọ́ láti ọdún Júbílì,+ iye tí wọ́n dá lé e kò ní yí pa dà. 18 Tó bá jẹ́ ẹ̀yìn ọdún Júbílì ló ya ilẹ̀ rẹ̀ sí mímọ́, kí àlùfáà fi iye ọdún tó ṣẹ́ kù kí ọdún Júbílì tó ń bọ̀ tó dé ṣírò owó rẹ̀ fún un, kó sì yọ kúrò nínú iye tí wọ́n dá lé e.+ 19 Àmọ́ tí ẹni tó ya ilẹ̀ náà sí mímọ́ bá tiẹ̀ fẹ́ rà á pa dà, ó gbọ́dọ̀ fi ìdá márùn-ún iye tí wọ́n dá lé e kún un, yóò sì di tirẹ̀. 20 Tí kò bá wá ra ilẹ̀ náà pa dà, tí wọ́n sì tà á fún ẹlòmíì, kò ní lè rà á pa dà mọ́. 21 Tí wọ́n bá yọ̀ǹda ilẹ̀ náà lọ́dún Júbílì, yóò di ohun mímọ́ fún Jèhófà, ilẹ̀ tí wọ́n yà sọ́tọ̀ fún un. Ó máa di ohun ìní àwọn àlùfáà.+
22 “‘Tí ẹnì kan bá ra ilẹ̀ kan, tí kì í ṣe ara ohun tó jogún,+ tó sì yà á sí mímọ́ fún Jèhófà, 23 kí àlùfáà bá a ṣírò owó rẹ̀ títí di ọdún Júbílì, kó sì san iye tí wọ́n dá lé e ní ọjọ́ yẹn.+ Ohun mímọ́ ló jẹ́ fún Jèhófà. 24 Ní ọdún Júbílì, ilẹ̀ náà yóò pa dà di ti ẹni tó tà á fún un, yóò di ti ẹni tó ni ilẹ̀ náà.+
25 “‘Ṣékélì ibi mímọ́ ni kí ẹ fi díwọ̀n gbogbo owó náà. Kí ṣékélì náà jẹ́ ogún (20) òṣùwọ̀n gérà.*
26 “‘Àmọ́, kí ẹnì kankan má ya àkọ́bí ẹran sí mímọ́, torí ti Jèhófà ni àkọ́bí tí ẹran bá bí.+ Ì báà jẹ́ akọ màlúù tàbí àgùntàn, Jèhófà ló ni ín.+ 27 Tó bá wà lára àwọn ẹran aláìmọ́, tó sì tún un rà pa dà gẹ́gẹ́ bí iye tí wọ́n dá lé e, kó fi ìdá márùn-ún rẹ̀ kún un.+ Àmọ́ tí kò bá rà á pa dà, iye tí wọ́n dá lé e ni kí wọ́n tà á.
28 “‘Àmọ́ tí ẹnì kan bá ti ya ohunkóhun sọ́tọ̀ pátápátá* fún Jèhófà látinú àwọn ohun tó ní, ì báà jẹ́ èèyàn tàbí ẹran tàbí ilẹ̀ tó jẹ́ tirẹ̀, kò gbọ́dọ̀ tà á tàbí kó rà á pa dà. Gbogbo ohun tí èèyàn bá ti yà sọ́tọ̀ jẹ́ ohun mímọ́ jù lọ fún Jèhófà.+ 29 Bákan náà, ẹ ò gbọ́dọ̀ ra ẹnikẹ́ni tí a máa pa run pa dà.+ Ṣe ni kí ẹ pa á.+
30 “‘Gbogbo ìdá mẹ́wàá+ ilẹ̀ náà jẹ́ ti Jèhófà, ì báà jẹ́ látinú irè oko ilẹ̀ náà tàbí èso igi. Ohun mímọ́ fún Jèhófà ni. 31 Tí ẹnì kan bá fẹ́ ra èyíkéyìí nínú ìdá mẹ́wàá rẹ̀ pa dà, kó fi ìdá márùn-ún rẹ̀ kún un. 32 Ní ti gbogbo ìdá mẹ́wàá ọ̀wọ́ ẹran àti agbo ẹran, gbogbo ohun tó bá kọjá lábẹ́ ọ̀pá olùṣọ́ àgùntàn, kí ẹran* kẹwàá di ohun mímọ́ fún Jèhófà. 33 Kó má yẹ̀ ẹ́ wò bóyá ó dáa tàbí kò dáa, kó má sì pààrọ̀ rẹ̀. Àmọ́ tó bá gbìyànjú láti pààrọ̀ rẹ̀ pẹ́nrẹ́n, èyí tó fẹ́ pààrọ̀ àti èyí tó fi pààrọ̀ yóò di ohun mímọ́.+ Kò gbọ́dọ̀ rà á pa dà.’”
34 Èyí ni àwọn àṣẹ tí Jèhófà pa fún Mósè ní Òkè Sínáì+ pé kó sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.
Ní Héb., “àwọn ọmọkùnrin Ísírẹ́lì.”
Tàbí “ọ̀rá tó yí kíndìnrín ká.”
Tàbí “tó tuni lójú.” Ní Héb., “atura.”
Tàbí “ọ̀rá tó yí kíndìnrín ká.”
Tàbí “tó tuni lójú.” Ní Héb., “atura.”
Tàbí “eérú ọlọ́ràá,” ìyẹn, eérú tí ọ̀rá tí wọ́n fi rúbọ ti rin.
Tàbí “tó tuni lójú.” Ní Héb., “atura.”
Tàbí “ọkàn.”
Tàbí “ohun ìrántí (ìṣàpẹẹrẹ) látinú rẹ̀.”
Tàbí “tó tuni lójú.” Ní Héb., “atura.”
Tàbí “ohun ìrántí (ìṣàpẹẹrẹ) látinú rẹ̀.”
Tàbí “tó tuni lójú.” Ní Héb., “atura.”
Tàbí “tó tuni lójú.” Ní Héb., “atura.”
Tàbí “ṣírí tútù.”
Tàbí “ohun ìrántí (ìṣàpẹẹrẹ) látinú rẹ̀.”
Tàbí “ẹbọ àlàáfíà.”
Tàbí “tó tuni lójú.” Ní Héb., “atura.”
Ní Héb., “búrẹ́dì,” ìyẹn, ìpín ti Ọlọ́run nínú ẹbọ ìrẹ́pọ̀ náà.
Tàbí “tó tuni lójú.” Ní Héb., “atura.”
Tàbí “ọkàn.”
Tàbí “eérú ọlọ́ràá,” ìyẹn, eérú tí ọ̀rá tí wọ́n fi rúbọ ti rin.
Tàbí “ọkàn.”
Tàbí “tó tuni lójú.” Ní Héb., “atura.”
Tàbí “ọkàn.”
Ní Héb., “ó gbọ́ ohùn ègún (ìbúra).” Ó lè jẹ́ ìkéde nípa ẹ̀ṣẹ̀ tí ẹnì kan dá tó ní nínú ègún tí wọ́n gé fún ẹni tó dẹ́ṣẹ̀ tàbí fún ẹni tí ọ̀rọ̀ náà ṣojú rẹ̀ tó bá kọ̀ láti jẹ́rìí sí i.
Tàbí “ọkàn.”
Tàbí “ọkàn.”
Ohun tó ṣeé ṣe kó túmọ̀ sí ni pé kò mú ẹ̀jẹ́ rẹ̀ ṣẹ.
Ìdá mẹ́wàá òṣùwọ̀n eéfà kan jẹ́ Lítà 2.2. Wo Àfikún B14.
Tàbí “ohun ìrántí (ìṣàpẹẹrẹ) látinú rẹ̀.”
Tàbí “ọkàn.”
Tàbí “ṣékélì mímọ́.”
Ṣékélì kan jẹ́ gíráàmù 11.4. Wo Àfikún B14.
Tàbí “ọkàn.”
Tàbí “ọkàn.”
Tàbí “aṣọ àtàtà.”
Tàbí “àwọ̀tẹ́lẹ̀.”
Tàbí “eérú ọlọ́ràá,” ìyẹn, eérú tí ọ̀rá tí wọ́n fi rúbọ ti rin.
Tàbí “tó tuni lójú.” Ní Héb., “atura.”
Tàbí “ohun ìrántí (ìṣàpẹẹrẹ) látinú rẹ̀.”
Tàbí “àwọn ọrẹ náà.”
Ìdá mẹ́wàá òṣùwọ̀n eéfà kan jẹ́ Lítà 2.2. Wo Àfikún B14.
Tàbí “tó tuni lójú.” Ní Héb., “atura.”
Tàbí “ọkàn.”
Tàbí “ọkàn.”
Tàbí “ọkàn.”
Tàbí “ọkàn.”
Tàbí “ọkàn.”
Tàbí “ọkàn èyíkéyìí.”
Tàbí “ọ̀já ìgbànú.”
Tàbí “adé mímọ́.”
Tàbí “fi.”
Tàbí “ọ̀rá tó yí kíndìnrín ká.”
Tàbí “tó tuni lójú.” Ní Héb., “atura.”
Tàbí “tó tuni lójú.” Ní Héb., “atura.”
Ní Héb., “fi kún ọwọ́ yín.”
Tàbí “ẹran tó ń rìn lórí ilẹ̀.”
Tàbí “alààyè ọkàn.”
Tàbí “gbogbo kòkòrò.”
Ní Héb., “aṣọ àpò ìdọ̀họ.”
Tàbí “ọkàn yín.”
Tàbí “ọkàn yín.”
Tàbí “alààyè ọkàn.”
Tàbí “ọkàn.”
Tàbí “Tí ọlẹ̀ bá sọ nínú obìnrin kan.”
Tàbí “kọ ọmọ náà nílà.”
Ní Héb., “awọ ara.”
Ọ̀rọ̀ Hébérù tí wọ́n tú sí “ẹ̀tẹ̀” ní ìtumọ̀ tó pọ̀, ó lè túmọ̀ sí oríṣiríṣi àrùn tó máa ń wà ní awọ ara, tó sì lè ran ẹlòmíì. Ó tún lè jẹ́ àwọn nǹkan tó máa ń yọ lára aṣọ tàbí lára ilé tó sì lè fa àrùn.
Tàbí “àrùn.”
Tàbí “lọ fara han àlùfáà lẹ́ẹ̀kejì.”
Tàbí “àrùn ẹni náà kò lè ranni.”
Tàbí “aṣọ àtàtà.”
Ìdá mẹ́ta nínú mẹ́wàá òṣùwọ̀n eéfà kan jẹ́ Lítà 6.6. Wo Àfikún B14.
Òṣùwọ̀n lọ́ọ̀gì kan jẹ́ Lítà 0.31. Wo Àfikún B14.
Ìdá mẹ́wàá òṣùwọ̀n eéfà kan jẹ́ Lítà 2.2. Wo Àfikún B14.
Ní Héb., “ẹ̀ṣẹ̀.”
Ní Héb., “ẹ̀ṣẹ̀.”
Ní Héb., “ẹran ara.”
Tàbí “àwọsánmà.”
Tàbí “aṣọ àtàtà.”
Tàbí “àwọ̀tẹ́lẹ̀.”
Tàbí “ìhòòhò.”
Ó ṣeé ṣe kó túmọ̀ sí “Ewúrẹ́ Tó Lọ.”
Tàbí “kó mú kí ẹnì kan wà ní sẹpẹ́.”
Ní Héb., “ẹran ara rẹ̀.”
Tàbí “ọkàn yín.” Kí èèyàn “pọ́n ara rẹ̀ lójú” sábà máa ń túmọ̀ sí kí èèyàn fi oríṣiríṣi nǹkan du ara rẹ̀, irú bíi kó gbààwẹ̀.
Tàbí “ọkàn yín.”
Ní Héb., “tí ẹ ó fi kún ọwọ́ rẹ̀.”
Tàbí “tó tuni lójú.” Ní Héb., “atura.”
Ní Héb., “àwọn ewúrẹ́.”
Tàbí “ọkàn.”
Tàbí “ọkàn.”
Tàbí “ọkàn yín.”
Tàbí “ọkàn.”
Tàbí “Ọkàn kankan.”
Tàbí “ọkàn.”
Tàbí “ọkàn.”
Tàbí “ọkàn.”
Tàbí “ọkàn èyíkéyìí.”
Ní Héb., “wẹ ẹran ara rẹ̀.”
Ní Héb., “láti ṣí i sí ìhòòhò,” ní ẹsẹ yìí àtàwọn ẹsẹ tó tẹ̀ lé e.
Ní Héb., “Ìhòòhò bàbá rẹ̀ ni.”
Ní Héb., “ṣí ìhòòhò.”
Ní Héb., “ìhòòhò arákùnrin rẹ ni.”
Tàbí “ìwà tó ń dójú tini; ìwà ìbàjẹ́.”
Tàbí “ọmọnìkejì rẹ; ọ̀rẹ́ rẹ.”
Tàbí “ya ọmọ rẹ kankan sọ́tọ̀ fún.”
Tàbí “ọkàn.”
Ní Héb., “bẹ̀rù.”
Tàbí “ọkàn.”
Tàbí “kó ohun tó bá ṣẹ́ kù lára.”
Tàbí “àwọn tí ìyà ń jẹ.”
Tàbí “pe ibi wá sórí.”
Ní Héb., “ẹ̀jẹ̀.”
Tàbí kó jẹ́, “O ò gbọ́dọ̀ máa wò tí ẹ̀mí ọmọnìkejì rẹ bá wà nínú ewu.”
Ní Héb., “tó jẹ́ aláìkọlà.”
Ní Héb., “aláìkọlà.”
Tàbí “gé.”
Tàbí “torí ọkàn kan.” Ní ẹsẹ yìí, ọ̀rọ̀ Hébérù náà neʹphesh ń tọ́ka sí ẹni tó ti kú.
Ní Héb., “bẹ̀rù.”
Ní Héb., “òṣùwọ̀n eéfà tó péye.” Wo Àfikún B14.
Ní Héb., “òṣùwọ̀n hínì tó péye.” Wo Àfikún B14.
Tàbí “ọkàn náà.”
Tàbí “pe ibi wá sórí.”
Ní Héb., “ṣí ìhòòhò.”
Tàbí “ìwà tó ń dójú tini; ìwà ìbàjẹ́.”
Ní Héb., “ṣí ìhòòhò.”
Ní Héb., “ṣí ìhòòhò.”
Ní Héb., “ṣí ìhòòhò.”
Tàbí “ọkàn yín.”
Tàbí “tó ní ẹ̀mí ìsọtẹ́lẹ̀.”
Tàbí “ọkàn.”
Tàbí “búrẹ́dì,” ó ń tọ́ka sí àwọn ẹbọ.
Ní Héb., “fi kún ọwọ́ rẹ̀.”
Tàbí “ọkàn èyíkéyìí tó ti kú.” Ní ẹsẹ yìí, ọ̀rọ̀ Hébérù náà neʹphesh jẹ mọ́ ọ̀rọ̀ Hébérù tó túmọ̀ sí “òkú.”
Ní Héb., “èso.”
Ní Héb., “èso.”
Ní Héb., “tàbí tí imú rẹ̀ là.”
Tàbí kó jẹ́, “ẹni tó rù kan eegun.”
Ní Héb., “èso.”
Ní Héb., “ya ara wọn sọ́tọ̀ kúrò lára.”
Tàbí “ọkàn.”
Tàbí “ọkàn kan.”
Tàbí “Ọkàn.”
Ní Héb., “Àjèjì kankan,” ìyẹn ẹni tí kì í ṣe ara ìdílé Áárónì.
Tàbí “ọkàn kan.”
Tàbí “fẹ́ àjèjì.”
Ní Héb., “àjèjì kankan,” ìyẹn ẹni tí kì í ṣe ara ìdílé Áárónì.
Tàbí “ògòdò.”
Ní Héb., “Láàárín ìrọ̀lẹ́ méjèèjì.”
Ìdá méjì nínú mẹ́wàá òṣùwọ̀n eéfà jẹ́ Lítà 4.4. Wo Àfikún B14.
Tàbí “tó tuni lójú.” Ní Héb., “atura.”
Òṣùwọ̀n hínì kan jẹ́ Lítà 3.67. Wo Àfikún B14.
Ìdá méjì nínú mẹ́wàá òṣùwọ̀n eéfà jẹ́ Lítà 4.4. Wo Àfikún B14.
Tàbí “tó tuni lójú.” Ní Héb., “atura.”
Tàbí “àwọn tí ìyà ń jẹ.”
Tàbí “ọkàn yín.” Kí èèyàn “pọ́n ara rẹ̀ lójú” sábà máa ń túmọ̀ sí kí èèyàn fi oríṣiríṣi nǹkan du ara rẹ̀, irú bíi kó gbààwẹ̀.
Tàbí “ọkàn èyíkéyìí.”
Tàbí kó jẹ́, “tí kò bá gbààwẹ̀.”
Tàbí “Ọkàn èyíkéyìí.”
Tàbí “ọkàn yín.”
Ìdá méjì nínú mẹ́wàá òṣùwọ̀n eéfà jẹ́ Lítà 4.4. Wo Àfikún B14.
Tàbí “ohun ìrántí (ìṣàpẹẹrẹ) látinú rẹ̀.”
Ìyẹn orúkọ Jèhófà, bó ṣe wà ní ẹsẹ 15 àti 16.
Tàbí “pe ibi wá sórí rẹ̀.”
Tàbí “kọ lu ọkàn èèyàn èyíkéyìí lọ́nà tó yọrí sí ikú.”
Tàbí “kọ lu ọkàn ẹran lọ́nà tó yọrí sí ikú.”
Tàbí “gba èlé gọbọi lọ́wọ́ rẹ̀.”
Ní Héb., “ọmọkùnrin.”
Tàbí “tó jẹ́ ẹ̀jẹ̀ rẹ̀.”
Ní Héb., “ọmọkùnrin.”
Ní Héb., “bẹ̀rù.”
Ní Héb., “yíjú.”
Ní Héb., “ọkàn mi.”
Tàbí “rìn pẹ̀lú orí yín lókè.”
Tàbí “ọkàn yín.”
Tàbí “ọkàn yín.”
Ní Héb., “ọ̀pá.” Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ àwọn ọ̀pá tí wọ́n fi ń tọ́jú búrẹ́dì.
Tàbí “oúnjẹ.”
Ó ṣeé ṣe kí ọ̀rọ̀ Hébérù yìí ní í ṣe pẹ̀lú ọ̀rọ̀ tí wọ́n ń lò fún “ìgbẹ́,” wọ́n sì máa ń lò ó fún ohun tí wọ́n bá kórìíra.
Tàbí “ọkàn mi.”
Tàbí “tó tuni lójú.” Ní Héb., “atura.”
Tàbí “pa sábáàtì mọ́.”
Tàbí “ọkàn wọn tó le;” “tí wọn ò dá bí ẹni dá adọ̀dọ́.”
Tàbí “ọkàn wọn.”
Tàbí “ọkàn.”
Ṣékélì kan jẹ́ gíráàmù 11.4. Wo Àfikún B14.
Tàbí “ṣékélì mímọ́.”
Hómérì kan jẹ́ òṣùwọ̀n tó gba Lítà 220. Wo Àfikún B14.
Gérà kan jẹ́ gíráàmù 0.57. Wo Àfikún B14.
Tàbí “fún ìparun.”
Tàbí “orí.”