DIUTARÓNÓMÌ
1 Èyí ni àwọn ọ̀rọ̀ tí Mósè bá gbogbo Ísírẹ́lì sọ ní agbègbè Jọ́dánì nínú aginjù, ní aṣálẹ̀ tó tẹ́jú níwájú Súfù, láàárín Páránì, Tófélì, Lábánì, Hásérótì àti Dísáhábù. 2 Ìrìn ọjọ́ mọ́kànlá (11) ni láti Hórébù sí Kadeṣi-bánéà+ tí wọ́n bá gba ọ̀nà Òkè Séírì. 3 Ní ọjọ́ kìíní, oṣù kọkànlá, ọdún ogójì,+ Mósè bá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì* sọ gbogbo ohun tí Jèhófà ní kó sọ fún wọn. 4 Èyí jẹ́ lẹ́yìn tó ṣẹ́gun Síhónì+ ọba àwọn Ámórì, tó ń gbé ní Hẹ́ṣíbónì àti Ógù+ ọba Báṣánì, tó ń gbé ní Áṣítárótì, ní Édíréì.+ 5 Ní agbègbè Jọ́dánì ní ilẹ̀ Móábù, Mósè bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàlàyé Òfin+ yìí, pé:
6 “Jèhófà Ọlọ́run wa sọ fún wa ní Hórébù pé, ‘Ẹ ti pẹ́ tó ní agbègbè olókè yìí.+ 7 Ẹ ṣẹ́rí pa dà, kí ẹ sì máa lọ sí agbègbè olókè àwọn Ámórì,+ kí ẹ forí lé ọ̀dọ̀ gbogbo àwọn tó yí wọn ká ní Árábà,+ agbègbè olókè, Ṣẹ́fẹ́là, Négébù àti etí òkun, + ilẹ̀ àwọn ọmọ Kénáánì àti Lẹ́bánónì,*+ títí dé odò ńlá, ìyẹn odò Yúfírétì.+ 8 Ẹ wò ó, mo ti fi ilẹ̀ náà síwájú yín. Ẹ wọ inú rẹ̀ lọ, kí ẹ sì gba ilẹ̀ tí Jèhófà búra pé òun máa fún àwọn bàbá yín, Ábúráhámù, Ísákì,+ Jékọ́bù+ àti àwọn àtọmọdọ́mọ* wọn lẹ́yìn wọn.’+
9 “Mo sọ fún yín nígbà yẹn pé, ‘Mi ò lè dá ẹrù yín gbé.+ 10 Jèhófà Ọlọ́run yín ti mú kí ẹ pọ̀, ẹ̀yin sì nìyí lónìí tí ẹ pọ̀ bí ìràwọ̀ ojú ọ̀run.+ 11 Kí Jèhófà Ọlọ́run àwọn baba ńlá yín mú kí ẹ pọ̀ ju báyìí lọ+ ní ìlọ́po ẹgbẹ̀rún, kí ó sì bù kún yín bó ṣe ṣèlérí fún yín gẹ́lẹ́.+ 12 Báwo ni màá ṣe dá ru àjàgà yín àti ẹrù yín pẹ̀lú gbogbo bí ẹ ṣe máa ń fa wàhálà?+ 13 Ẹ yan àwọn ọkùnrin tó jẹ́ ọlọ́gbọ́n àti olóye, tí wọ́n sì ní ìrírí látinú àwọn ẹ̀yà yín, màá sì fi wọ́n ṣe olórí yín.’+ 14 Ẹ fèsì pé, ‘Ohun tí o ní ká ṣe dáa.’ 15 Torí náà, mo mú àwọn olórí ẹ̀yà yín, àwọn ọkùnrin tó jẹ́ ọlọ́gbọ́n, tí wọ́n sì ní ìrírí, mo yàn wọ́n ṣe olórí yín, olórí ẹgbẹẹgbẹ̀rún, olórí ọgọ́rọ̀ọ̀rún, olórí àràádọ́ta, olórí àwọn mẹ́wàá-mẹ́wàá àti àwọn aṣojú nínú àwọn ẹ̀yà yín.+
16 “Nígbà yẹn, mo sọ fún àwọn onídàájọ́ yín pé, ‘Tí ẹ bá ń gbọ́ ẹjọ́ láàárín àwọn arákùnrin yín, kí ẹ máa fi òdodo ṣèdájọ́+ láàárín ọkùnrin kan àti arákùnrin rẹ̀ tàbí àjèjì tí ẹ jọ ń gbé.+ 17 Ẹ ò gbọ́dọ̀ gbè sápá kan nínú ìdájọ́.+ Bí ẹ ṣe máa gbọ́ ẹjọ́ ẹni tó kéré ni kí ẹ ṣe gbọ́ ti ẹni ńlá.+ Ẹ ò gbọ́dọ̀ jẹ́ kí àwọn èèyàn dẹ́rù bà yín,+ torí Ọlọ́run ló ni ìdájọ́;+ tí ẹjọ́ kan bá sì le jù fún yín, kí ẹ gbé e wá sọ́dọ̀ mi, màá sì gbọ́ ọ.’+ 18 Nígbà yẹn, mo sọ gbogbo ohun tó yẹ kí ẹ ṣe fún yín.
19 “Lẹ́yìn náà, a kúrò ní Hórébù, a sì kọjá ní gbogbo aginjù tí ó tóbi tó sì ń bani lẹ́rù yẹn,+ èyí tí ẹ rí lójú ọ̀nà tó lọ sí agbègbè olókè àwọn Ámórì,+ bí Jèhófà Ọlọ́run wa ṣe pàṣẹ fún wa gẹ́lẹ́, a sì wá dé Kadeṣi-bánéà.+ 20 Mo wá sọ fún yín pé, ‘Ẹ ti dé agbègbè olókè àwọn Ámórì, èyí tí Jèhófà Ọlọ́run wa fẹ́ fún wa. 21 Wò ó, Jèhófà Ọlọ́run rẹ ti fún ọ ní ilẹ̀ náà. Gòkè lọ, kí o sì gbà á bí Jèhófà Ọlọ́run àwọn baba ńlá rẹ ṣe sọ fún ọ gẹ́lẹ́.+ Má bẹ̀rù, má sì fòyà.’
22 “Àmọ́ gbogbo yín wá bá mi, ẹ sì sọ pé, ‘Jẹ́ ká rán àwọn ọkùnrin lọ ṣáájú wa, kí wọ́n lè bá wa wo ilẹ̀ náà, kí wọ́n sì pa dà wá jábọ̀ fún wa, ká lè mọ ọ̀nà tí a máa gbà àtàwọn ìlú tó wà lọ́nà.’+ 23 Àbá yẹn dáa lójú mi, mo sì yan ọkùnrin méjìlá (12) lára yín, ẹnì kan látinú ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan.+ 24 Wọ́n gbéra, wọ́n sì gòkè lọ sí agbègbè olókè náà,+ wọ́n dé Àfonífojì Éṣíkólì, wọ́n sì ṣe amí ilẹ̀ náà. 25 Wọ́n mú lára èso ilẹ̀ náà, wọ́n sì kó o wá fún wa, wọ́n pa dà wá jábọ̀ fún wa pé, ‘Ilẹ̀ tí Jèhófà Ọlọ́run wa fẹ́ fún wa dáa.’+ 26 Àmọ́ ẹ kọ̀ láti gòkè lọ, ẹ sì kọ̀ láti tẹ̀ lé àṣẹ Jèhófà Ọlọ́run yín.+ 27 Ẹ̀ ń ráhùn ṣáá nínú àwọn àgọ́ yín, ẹ sì ń sọ pé, ‘Torí Jèhófà kórìíra wa ló ṣe mú wa kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì láti fi wá lé àwọn Ámórì lọ́wọ́, kí wọ́n lè pa wá run. 28 Báwo ni ibi tí à ń lọ ṣe rí? Àwọn arákùnrin wa mú kí ẹ̀rù bà wá,*+ wọ́n sọ pé: “Àwọn èèyàn náà lágbára, wọ́n sì ga jù wá lọ, àwọn ìlú wọn tóbi, wọ́n sì mọ odi rẹ̀ kan ọ̀run,*+ a sì rí àwọn ọmọ Ánákímù+ níbẹ̀.”’
29 “Mo wá sọ fún yín pé, ‘Ẹ má ṣe jẹ́ kí jìnnìjìnnì bò yín, ẹ má sì jẹ́ kí ẹ̀rù wọn bà yín.+ 30 Jèhófà Ọlọ́run yín máa lọ níwájú yín, ó sì máa jà fún yín,+ bó ṣe jà fún yín ní Íjíbítì tí ẹ̀yin náà sì fi ojú ara yín rí i.+ 31 Ẹ sì rí i bí Jèhófà Ọlọ́run yín ṣe gbé yín nínú aginjù, bí bàbá ṣe ń gbé ọmọ rẹ̀, tó sì ń gbé yín kiri gbogbo ibi tí ẹ lọ títí ẹ fi dé ibí yìí.’ 32 Àmọ́ pẹ̀lú gbogbo èyí, ẹ ò gba Jèhófà Ọlọ́run yín gbọ́,+ 33 ẹni tó ń ṣáájú yín lójú ọ̀nà, láti wá ibi tí ẹ lè pàgọ́ sí. Ó ń fara hàn yín nípasẹ̀ iná ní òru àti nípasẹ̀ ìkùukùu* ní ọ̀sán, láti fi ọ̀nà tí ẹ máa gbà hàn yín.+
34 “Ní gbogbo ìgbà yẹn, Jèhófà gbọ́ ohun tí ẹ̀ ń sọ, inú sì bí i gidigidi, ó wá búra pé,+ 35 ‘Ìkankan nínú àwọn èèyàn yìí tí wọ́n wà lára ìran búburú yìí kò ní rí ilẹ̀ dáradára tí mo búra pé màá fún àwọn bàbá yín,+ 36 àfi Kélẹ́bù ọmọ Jéfúnè. Òun máa rí i, mo sì máa fún òun àti àwọn ọmọ rẹ̀ ní ilẹ̀ tó rìn lórí rẹ̀, torí pé ó fi gbogbo ọkàn rẹ̀ tẹ̀ lé Jèhófà.*+ 37 (Torí yín ni Jèhófà tiẹ̀ ṣe bínú sí mi, ó ní, “Ìwọ náà ò ní wọ ibẹ̀.+ 38 Jóṣúà ọmọ Núnì, tó máa ń dúró níwájú rẹ+ ló máa wọ ilẹ̀ náà.+ Sọ ọ́ di alágbára,*+ torí òun ló máa mú kí Ísírẹ́lì jogún rẹ̀.”) 39 Àmọ́, àwọn ọmọ yín tí ẹ sọ pé wọ́n máa kó lẹ́rú+ àti àwọn ọmọ yín tí wọn ò mọ rere yàtọ̀ sí búburú lónìí ni wọ́n máa wọ ibẹ̀, àwọn ni màá sì fún ní ilẹ̀ náà kó lè di tiwọn.+ 40 Ní tiyín, ẹ ṣẹ́rí pa dà, kí ẹ gba ọ̀nà Òkun Pupa lọ sí aginjù.’+
41 “Ẹ wá sọ fún mi pé, ‘A ti ṣẹ Jèhófà. A máa gòkè lọ bá wọn jà báyìí, bí Jèhófà Ọlọ́run wa ṣe pa á láṣẹ fún wa gẹ́lẹ́!’ Kálukú yín wá múra ogun, ẹ sì rò pé bẹ́ẹ̀ ló ṣe máa rọrùn tó láti gun òkè náà lọ.+ 42 Àmọ́ Jèhófà sọ fún mi pé, ‘Sọ fún wọn pé: “Ẹ ò gbọ́dọ̀ gòkè lọ jà, torí mi ò ní bá yín lọ.+ Tí ẹ bá lọ, àwọn ọ̀tá yín máa ṣẹ́gun yín.”’ 43 Mo wá bá yín sọ̀rọ̀, àmọ́ ẹ ò gbọ́. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe lẹ kẹ̀yìn sí àṣẹ Jèhófà, ẹ sì ṣorí kunkun* pé ẹ máa gun òkè náà lọ. 44 Àwọn Ámórì tí wọ́n ń gbé ní òkè náà sì jáde wá pàdé yín, wọ́n lé yín dà nù bí oyin ṣe máa ń ṣe, wọ́n sì tú yín ká láti Séírì títí lọ dé Hóómà. 45 Ẹ wá pa dà, ẹ sì bẹ̀rẹ̀ sí í sunkún níwájú Jèhófà, àmọ́ Jèhófà kò fetí sí yín, kò sì dá yín lóhùn. 46 Ìdí nìyẹn tí iye ọjọ́ tí ẹ fi gbé ní Kádéṣì fi pọ̀ tó bẹ́ẹ̀.
2 “Lẹ́yìn náà, a ṣẹ́rí pa dà, a sì gba ọ̀nà Òkun Pupa lọ sí aginjù, bí Jèhófà ṣe sọ fún mi gẹ́lẹ́,+ ọ̀pọ̀ ọjọ́ la sì fi rìn yí ká Òkè Séírì. 2 Níkẹyìn, Jèhófà sọ fún mi pé, 3 ‘Èyí tí ẹ rìn yí ká òkè yìí tó. Ó yá, ẹ yí sí apá àríwá. 4 Kí o sì pàṣẹ fún àwọn èèyàn náà pé: “Ààlà ilẹ̀ àwọn arákùnrin yín, àwọn àtọmọdọ́mọ Ísọ̀,+ tí wọ́n ń gbé ní Séírì,+ lẹ máa gbà kọjá, ẹ̀rù yín á sì máa bà wọ́n,+ torí náà, ẹ ṣọ́ra gidigidi. 5 Ẹ má ṣe bá wọn fa wàhálà kankan,* torí mi ò ní fún yín ní ìkankan lára ilẹ̀ wọn, bí ò tiẹ̀ ju ìwọ̀n àtẹ́lẹsẹ̀ kan lọ, torí mo ti fún Ísọ̀ ní Òkè Séírì kó lè di tirẹ̀.+ 6 Kí ẹ san owó oúnjẹ tí ẹ bá jẹ fún wọn, kí ẹ sì san owó omi tí ẹ bá mu.+ 7 Torí Jèhófà Ọlọ́run rẹ ti bù kún ọ nínú gbogbo ohun tí o ṣe. Ó mọ gbogbo bí o ṣe ń rìn nínú aginjù tó tóbi yìí dáadáa. Jèhófà Ọlọ́run rẹ ti wà pẹ̀lú rẹ jálẹ̀ ogójì (40) ọdún yìí, o ò sì ṣaláìní ohunkóhun.”’+ 8 Torí náà, a gba ọ̀dọ̀ àwọn arákùnrin wa kọjá, àwọn àtọmọdọ́mọ Ísọ̀,+ tí wọ́n ń gbé ní Séírì, a ò gba ọ̀nà Árábà, Élátì àti Esioni-gébérì.+
“A wá yí gba ọ̀nà aginjù Móábù.+ 9 Jèhófà wá sọ fún mi pé, ‘Má ṣe bá Móábù fa wàhálà kankan, má sì bá wọn jagun, torí mi ò ní fún ọ ní ìkankan lára ilẹ̀ rẹ̀ pé kó di tìrẹ, torí mo ti fún àwọn àtọmọdọ́mọ Lọ́ọ̀tì ní Árì kó lè di tiwọn.+ 10 (Àwọn Émímù+ ló ń gbé ibẹ̀ tẹ́lẹ̀, èèyàn ńlá ni wọ́n, wọ́n pọ̀ gan-an, wọ́n sì ga bí àwọn Ánákímù. 11 Àwọn Réfáímù+ náà rí bí àwọn Ánákímù,+ àwọn ọmọ Móábù sì máa ń pè wọ́n ní Émímù. 12 Séírì ni àwọn Hórì+ ń gbé tẹ́lẹ̀, àmọ́ àwọn àtọmọdọ́mọ Ísọ̀ lé wọn kúrò, wọ́n pa wọ́n run, wọ́n sì wá ń gbé ilẹ̀ wọn,+ ohun tí Ísírẹ́lì máa ṣe sí ilẹ̀ tó jẹ́ tiwọn nìyẹn, èyí tó dájú pé Jèhófà máa fún wọn.) 13 Ó yá, lọ sọdá Àfonífojì Séréédì.’ Bí a ṣe lọ sọdá Àfonífojì Séréédì+ nìyẹn. 14 Ọdún méjìdínlógójì (38) la fi rìn láti Kadeṣi-bánéà títí a fi sọdá Àfonífojì Séréédì, títí gbogbo ìran àwọn ọkùnrin ogun fi pa run láàárín àpéjọ, bí Jèhófà ṣe búra fún wọn gẹ́lẹ́.+ 15 Jèhófà fi ọwọ́ rẹ̀ jẹ wọ́n níyà kó lè pa wọ́n run láàárín àpéjọ náà títí wọ́n fi ṣègbé.+
16 “Gbàrà tí gbogbo àwọn ọkùnrin ogun ti kú tán láàárín àwọn èèyàn náà,+ 17 Jèhófà tún sọ fún mi pé, 18 ‘Lónìí, kí ẹ gba ilẹ̀ Móábù kọjá, ìyẹn Árì. 19 Tí o bá ti sún mọ́ ọ̀dọ̀ àwọn ọmọ Ámónì, má yọ wọ́n lẹ́nu, má sì múnú bí wọn, torí mi ò ní fún ọ ní ìkankan lára ilẹ̀ àwọn ọmọ Ámónì kó lè di tìrẹ, nítorí mo ti fún àwọn àtọmọdọ́mọ Lọ́ọ̀tì kó lè di tiwọn.+ 20 Ilẹ̀ àwọn Réfáímù+ ni wọ́n máa ń ka ibí yìí náà sí tẹ́lẹ̀. (Ibẹ̀ ni àwọn Réfáímù ń gbé tẹ́lẹ̀, àwọn ọmọ Ámónì sì máa ń pè wọ́n ní Sámúsúmímù. 21 Èèyàn ńlá ni wọ́n, wọ́n pọ̀ gan-an, wọ́n sì ga bí àwọn Ánákímù;+ àmọ́ Jèhófà pa wọ́n run níwájú àwọn ọmọ Ámónì, wọ́n lé wọn jáde, wọ́n sì ń gbé ilẹ̀ wọn. 22 Ohun tó ṣe fún àwọn àtọmọdọ́mọ Ísọ̀ tí wọ́n ń gbé ní Séírì+ báyìí nìyẹn, nígbà tó pa àwọn Hórì+ run níwájú wọn, kí wọ́n lè lé wọn kúrò, kí wọ́n sì máa gbé ilẹ̀ wọn títí di òní yìí. 23 Ní ti àwọn Áfímù, ibi tí wọ́n ń gbé nasẹ̀ dé Gásà,+ títí àwọn Káfítórímù tí wọ́n wá láti Káfítórì*+ fi pa wọ́n run, tí wọ́n sì ń gbé ilẹ̀ wọn.)
24 “‘Ẹ dìde, kí ẹ sì rí i pé ẹ sọdá Àfonífojì Áánónì.+ Wò ó, mo ti fi Síhónì+ ọba Hẹ́ṣíbónì, tó jẹ́ Ámórì lé yín lọ́wọ́. Torí náà, ẹ bẹ̀rẹ̀ sí í gba ilẹ̀ rẹ̀, kí ẹ sì bá a jagun. 25 Lónìí yìí, màá mú kí ẹ̀rù yín máa ba gbogbo èèyàn tó wà lábẹ́ ọ̀run tí wọ́n bá gbọ́ ìròyìn nípa yín. Ọkàn wọn kò ní balẹ̀, jìnnìjìnnì á sì bò wọ́n* torí yín.’+
26 “Mo wá ní kí àwọn ìránṣẹ́ láti aginjù Kédémótì+ lọ jíṣẹ́ àlàáfíà+ yìí fún Síhónì ọba Hẹ́ṣíbónì pé, 27 ‘Jẹ́ kí n gba ilẹ̀ rẹ kọjá. Mi ò ní kọjá ojú ọ̀nà, mi ò sì ní yà sí ọ̀tún tàbí òsì.+ 28 Oúnjẹ àti omi tí o bá tà fún mi nìkan ni màá jẹ tí màá sì mu. Ṣáà jẹ́ kí n fi ẹsẹ̀ mi rìn kọjá, 29 títí màá fi sọdá Jọ́dánì sí ilẹ̀ tí Jèhófà Ọlọ́run wa fẹ́ fún wa. Ohun tí àwọn àtọmọdọ́mọ Ísọ̀ tí wọ́n ń gbé ní Séírì àtàwọn ọmọ Móábù tí wọ́n ń gbé ní Árì ṣe fún mi nìyẹn.’ 30 Àmọ́ Síhónì ọba Hẹ́ṣíbónì kò jẹ́ ká kọjá, torí Jèhófà Ọlọ́run rẹ gbà á láyè pé kó ṣorí kunkun,+ kí ọkàn rẹ̀ sì le, kó lè fi í lé ọ lọ́wọ́ bó ṣe rí báyìí. +
31 “Jèhófà wá sọ fún mi pé, ‘Wò ó, mo ti ń fi Síhónì àti ilẹ̀ rẹ̀ lé ọ lọ́wọ́. Bẹ̀rẹ̀ sí í gba ilẹ̀ rẹ̀.’+ 32 Nígbà tí Síhónì àti gbogbo èèyàn rẹ̀ jáde wá gbógun jà wá ní Jáhásì,+ 33 Jèhófà Ọlọ́run wa fi í lé wa lọ́wọ́, a sì ṣẹ́gun òun àtàwọn ọmọ rẹ̀ pẹ̀lú gbogbo èèyàn rẹ̀. 34 A gba gbogbo ìlú rẹ̀ nígbà yẹn, a sì pa gbogbo ìlú náà run, títí kan àwọn ọkùnrin, àwọn obìnrin àtàwọn ọmọdé. A ò dá ẹnikẹ́ni sí.+ 35 Àwọn ẹran ọ̀sìn nìkan la kó bọ̀ láti ogun pẹ̀lú àwọn ẹrù tí a kó láti àwọn ìlú tí a ṣẹ́gun. 36 Láti Áróérì,+ èyí tó wà ní etí Àfonífojì Áánónì, (títí kan ìlú tó wà ní àfonífojì náà), títí dé Gílíádì, kò sí ìlú tí apá wa ò ká. Gbogbo wọn ni Jèhófà Ọlọ́run wa fi lé wa lọ́wọ́.+ 37 Àmọ́, ẹ ò sún mọ́ ilẹ̀ àwọn ọmọ Ámónì,+ gbogbo etí Àfonífojì Jábókù+ àtàwọn ìlú tó wà ní agbègbè olókè àti gbogbo ibi tí Jèhófà Ọlọ́run wa kà léèwọ̀.
3 “Lẹ́yìn náà, a pa dà, a sì lọ gba Ọ̀nà Báṣánì. Ógù ọba Báṣánì àti gbogbo àwọn èèyàn rẹ̀ sì jáde wá gbéjà kò wá ní Édíréì.+ 2 Jèhófà wá sọ fún mi pé, ‘Má bẹ̀rù rẹ̀, torí màá fi òun àti gbogbo èèyàn rẹ̀ àti ilẹ̀ rẹ̀ lé ọ lọ́wọ́; ohun tí o sì ṣe sí Síhónì, ọba àwọn Ámórì tó gbé ní Hẹ́ṣíbónì ni wàá ṣe sí i.’ 3 Torí náà, Jèhófà Ọlọ́run wa tún fi Ógù ọba Báṣánì àti gbogbo èèyàn rẹ̀ lé wa lọ́wọ́, a sì bá a jà títí ìkankan nínú àwọn èèyàn rẹ̀ ò fi ṣẹ́ kù. 4 A wá gba gbogbo ìlú rẹ̀. Kò sí ìlú tí a kò gbà lọ́wọ́ wọn, ọgọ́ta (60) ìlú ní gbogbo agbègbè Ágóbù, ilẹ̀ ọba Ógù ní Báṣánì.+ 5 Gbogbo ìlú yìí ni wọ́n mọ odi gàgàrà yí ká, wọ́n ní ẹnubodè àtàwọn ọ̀pá ìdábùú, pẹ̀lú ọ̀pọ̀lọpọ̀ àrọko. 6 Àmọ́, a pa wọ́n run,+ bí a ṣe ṣe sí Síhónì ọba Hẹ́ṣíbónì gẹ́lẹ́, tí a pa gbogbo ìlú wọn run, títí kan àwọn ọkùnrin, obìnrin àtàwọn ọmọdé.+ 7 A sì kó gbogbo ẹran ọ̀sìn àtàwọn ohun tí a rí nínú ìlú náà fún ara wa.
8 “Ìgbà yẹn la gba ilẹ̀ ọba àwọn Ámórì méjèèjì + tí wọ́n wà ní agbègbè Jọ́dánì, láti Àfonífojì Áánónì títí dé Òkè Hámónì+ 9 (òkè yìí ni àwọn ọmọ Sídónì máa ń pè ní Síríónì, tí àwọn Ámórì sì máa ń pè ní Sénírì), 10 gbogbo ìlú tó wà lórí ilẹ̀ tó tẹ́jú,* gbogbo Gílíádì àti gbogbo Báṣánì títí dé Sálékà àti Édíréì,+ àwọn ìlú tó jẹ́ ti ilẹ̀ ọba Ógù ní Báṣánì. 11 Ógù ọba Báṣánì ló ṣẹ́ kù nínú àwọn Réfáímù. Irin* ni wọ́n fi ṣe àga ìgbókùú* rẹ̀, ó ṣì wà ní Rábà ti àwọn ọmọ Ámónì. Gígùn rẹ̀ jẹ́ ìgbọ̀nwọ́* mẹ́sàn-án, fífẹ̀ rẹ̀ sì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́rin, wọ́n lo ìgbọ̀nwọ́ tó péye. 12 Nígbà yẹn, a gba ilẹ̀ yìí: láti Áróérì,+ èyí tó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ Àfonífojì Áánónì àti ìdajì agbègbè olókè Gílíádì, mo sì ti fún àwọn ọmọ Rúbẹ́nì àti àwọn ọmọ Gádì+ ní àwọn ìlú rẹ̀. 13 Mo tún ti fún ààbọ̀ ẹ̀yà Mánásè+ ní ibi tó ṣẹ́ kù ní Gílíádì àti gbogbo Báṣánì tó jẹ́ ilẹ̀ ọba Ógù. Gbogbo agbègbè Ágóbù, tó jẹ́ ti Báṣánì, ni wọ́n mọ̀ sí ilẹ̀ àwọn Réfáímù.
14 “Jáírì+ ọmọ Mánásè gba gbogbo agbègbè Ágóbù+ títí dé ààlà àwọn ará Géṣúrì àti àwọn ará Máákátì,+ ó sì sọ àwọn abúlé Báṣánì yẹn ní orúkọ ara rẹ̀, ìyẹn Hafotu-jáírì*+ títí di òní olónìí. 15 Mo tún ti fún Mákírù ní Gílíádì.+ 16 Mo sì ti fún àwọn ọmọ Rúbẹ́nì àti àwọn ọmọ Gádì+ ní Gílíádì títí dé Àfonífojì Áánónì, àárín àfonífojì náà sì ni ààlà rẹ̀, títí lọ dé Jábókù, àfonífojì tó jẹ́ ààlà àwọn ọmọ Ámónì, 17 pẹ̀lú Árábà àti Jọ́dánì àti ààlà náà, láti Kínérétì sí Òkun Árábà, Òkun Iyọ̀,* ní ìsàlẹ̀ àwọn gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ Písígà sí apá ìlà oòrùn.+
18 “Mo wá pa àṣẹ yìí fún yín pé: ‘Jèhófà Ọlọ́run yín ti fún yín ní ilẹ̀ yìí kó lè di tiyín. Kí gbogbo ọkùnrin yín tó jẹ́ akọni gbé ohun ìjà, kí wọ́n sì sọdá níwájú àwọn arákùnrin yín, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.+ 19 Àwọn ìyàwó yín àti àwọn ọmọ yín nìkan ni yóò máa gbé inú àwọn ìlú tí mo fún yín, títí kan àwọn ẹran ọ̀sìn yín (mo mọ̀ dáadáa pé ẹ ní ẹran ọ̀sìn tó pọ̀), 20 títí Jèhófà fi máa fún àwọn arákùnrin yín ní ìsinmi, bíi tiyín, tí wọ́n á sì gba ilẹ̀ tí Jèhófà Ọlọ́run yín máa fún wọn ní òdìkejì Jọ́dánì. Lẹ́yìn náà, kí kálukú yín pa dà sí ilẹ̀ rẹ̀ tí mo fún yín.’+
21 “Mo pa àṣẹ yìí fún Jóṣúà+ nígbà yẹn pé: ‘O ti fi ojú ara rẹ rí ohun tí Jèhófà Ọlọ́run yín ṣe sí àwọn ọba méjì yìí. Ohun kan náà ni Jèhófà máa ṣe sí gbogbo ìjọba tí o máa bá pàdé tí o bá sọdá.+ 22 Ẹ ò gbọ́dọ̀ bẹ̀rù wọn, torí Jèhófà Ọlọ́run yín ló ń jà fún yín.’+
23 “Nígbà yẹn, mo bẹ Jèhófà pé, 24 ‘Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ, o ti ń fi títóbi rẹ àti ọwọ́ agbára rẹ han ìránṣẹ́ rẹ,+ àbí ọlọ́run wo ní ọ̀run tàbí ní ayé ló ń ṣe àwọn iṣẹ́ àrà bíi tìrẹ?+ 25 Jọ̀ọ́, jẹ́ kí n sọdá, kí n sì rí ilẹ̀ dáradára tó wà ní òdìkejì Jọ́dánì, agbègbè olókè tó dáa yìí àti Lẹ́bánónì.’+ 26 Àmọ́ Jèhófà ṣì ń bínú sí mi gidigidi nítorí yín,+ kò sì dá mi lóhùn. Kàkà bẹ́ẹ̀, ṣe ni Jèhófà sọ fún mi pé, ‘Ó tó gẹ́ẹ́! O ò gbọ́dọ̀ bá mi sọ̀rọ̀ yìí mọ́. 27 Gun orí Písígà lọ,+ kí o wo ìwọ̀ oòrùn, àríwá, gúúsù àti ìlà oòrùn, kí o sì fi ojú ara rẹ rí ilẹ̀ náà, torí pé o ò ní sọdá Jọ́dánì yìí.+ 28 Fa iṣẹ́ lé Jóṣúà lọ́wọ́,+ kí o fún un ní ìṣírí, kí o sì mú un lọ́kàn le, torí òun ló máa kó àwọn èèyàn yìí sọdá,+ òun ló sì máa mú kí wọ́n jogún ilẹ̀ tí wàá rí.’ 29 Ìgbà tí à ń gbé ní àfonífojì tó wà níwájú Bẹti-péórì+ ni gbogbo èyí ṣẹlẹ̀.
4 “Ní báyìí, ẹ̀yin ọmọ Ísírẹ́lì, ẹ fetí sí àwọn ìlànà àti àwọn ìdájọ́ tí mò ń kọ́ yín láti pa mọ́, kí ẹ lè máa wà láàyè,+ kí ẹ lè wọ ilẹ̀ tí Jèhófà Ọlọ́run àwọn baba ńlá yín máa fún yín, kí ẹ sì gbà á. 2 Ẹ ò gbọ́dọ̀ fi kún ọ̀rọ̀ tí mò ń pa láṣẹ fún yín, ẹ ò sì gbọ́dọ̀ yọ kúrò lára rẹ̀,+ kí ẹ lè máa tẹ̀ lé àwọn àṣẹ Jèhófà Ọlọ́run yín tí mò ń pa láṣẹ fún yín.
3 “Ẹ ti fi ojú ara yín rí ohun tí Jèhófà ṣe nínú ọ̀rọ̀ Báálì Péórì; gbogbo ọkùnrin tó tọ Báálì Péórì+ lẹ́yìn ni Jèhófà Ọlọ́run yín pa run kúrò láàárín yín. 4 Àmọ́ gbogbo ẹ̀yin tí ẹ rọ̀ mọ́ Jèhófà Ọlọ́run yín lẹ wà láàyè lónìí. 5 Ẹ wò ó, mo ti kọ́ yín ní àwọn ìlànà àti àwọn ìdájọ́,+ bí Jèhófà Ọlọ́run mi ṣe pa á láṣẹ fún mi gẹ́lẹ́, kí ẹ lè máa pa wọ́n mọ́ ní ilẹ̀ tí ẹ máa gbà. 6 Kí ẹ rí i pé ẹ̀ ń pa wọ́n mọ́,+ torí èyí máa fi hàn pé ẹ jẹ́ ọlọ́gbọ́n+ àti olóye+ lójú àwọn èèyàn tó máa gbọ́ nípa gbogbo ìlànà yìí, wọ́n á sì sọ pé, ‘Ó dájú pé ọlọ́gbọ́n àti olóye ni àwọn èèyàn orílẹ̀-èdè ńlá yìí.’+ 7 Orílẹ̀-èdè ńlá wo ni àwọn ọlọ́run rẹ̀ sún mọ́ ọn bíi ti Jèhófà Ọlọ́run wa nígbàkigbà tí a bá ké pè é?+ 8 Orílẹ̀-èdè ńlá wo ló sì ní àwọn ìlànà òdodo àti àwọn ìdájọ́ bíi ti gbogbo Òfin yìí tí mò ń fi sí iwájú yín lónìí?+
9 “Ṣáà máa kíyè sára, kí o sì máa ṣọ́ra gan-an,* kí o má bàa gbàgbé àwọn ohun tí o fi ojú rẹ rí, kí wọ́n má bàa kúrò lọ́kàn rẹ ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ. Kí o sì tún jẹ́ kí àwọn ọmọ rẹ àti àwọn ọmọ ọmọ rẹ mọ̀ nípa wọn.+ 10 Ní ọjọ́ tí o dúró níwájú Jèhófà Ọlọ́run rẹ ní Hórébù, Jèhófà sọ fún mi pé, ‘Pe àwọn èèyàn náà jọ sọ́dọ̀ mi kí n lè mú kí wọ́n gbọ́ àwọn ọ̀rọ̀ mi,+ kí wọ́n lè kọ́ láti máa bẹ̀rù mi+ ní gbogbo ọjọ́ tí wọ́n á fi wà láàyè lórí ilẹ̀, kí wọ́n sì lè kọ́ àwọn ọmọ wọn.’+
11 “Ẹ wá sún mọ́ tòsí òkè náà, ẹ sì dúró sí ìsàlẹ̀ rẹ̀, òkè náà sì ń yọ iná títí dé ọ̀run;* òkùnkùn ṣú, ìkùukùu* yọ, ojú ọjọ́ sì ṣú dùdù.+ 12 Jèhófà wá bẹ̀rẹ̀ sí í bá yín sọ̀rọ̀ látinú iná náà.+ Ẹ̀ ń gbọ́ tí ẹnì kan ń sọ̀rọ̀, àmọ́ ẹ ò rí ẹnì kankan,+ ohùn nìkan lẹ̀ ń gbọ́.+ 13 Ó sì kéde májẹ̀mú rẹ̀ fún yín,+ èyí tó pa láṣẹ fún yín pé kí ẹ máa pa mọ́, ìyẹn Òfin Mẹ́wàá.*+ Lẹ́yìn náà, ó kọ ọ́ sórí wàláà òkúta méjì.+ 14 Nígbà yẹn, Jèhófà pàṣẹ fún mi pé kí n kọ́ yín ní àwọn ìlànà àti àwọn ìdájọ́ tí ẹ ó máa pa mọ́ ní ilẹ̀ tí ẹ fẹ́ lọ gbà.
15 “Torí náà, ẹ ṣọ́ra gidigidi,* torí pé ẹ ò rí ẹnikẹ́ni lọ́jọ́ tí Jèhófà bá yín sọ̀rọ̀ ní Hórébù láti àárín iná náà, 16 kí ẹ má bàa hùwàkiwà nípa gbígbẹ́ ère èyíkéyìí tó jọ ohunkóhun fún ara yín, ohun tó rí bí akọ tàbí abo,+ 17 ohun tó rí bí ẹranko èyíkéyìí ní ayé, bí ẹyẹ tó ń fò lójú ọ̀run,+ 18 bí ohunkóhun tó ń rákò lórí ilẹ̀ tàbí tó rí bí ẹja èyíkéyìí nínú omi lábẹ́ ilẹ̀.+ 19 Tí o bá wá yíjú sókè wo ọ̀run, tí o sì rí oòrùn, òṣùpá àti àwọn ìràwọ̀, gbogbo ọmọ ogun ọ̀run, o ò gbọ́dọ̀ jẹ́ kí ọkàn rẹ fà sí wọn débi pé o máa forí balẹ̀ fún wọn, tí o sì máa sìn wọ́n.+ Gbogbo èèyàn lábẹ́ ọ̀run ni Jèhófà Ọlọ́run rẹ fi wọ́n fún. 20 Àmọ́ ẹ̀yin ni Jèhófà mú jáde nínú iná ìléru tí wọ́n ti ń yọ́ irin, kúrò nílẹ̀ Íjíbítì, kí ẹ lè di ohun ìní rẹ̀*+ bí ẹ ṣe jẹ́ lónìí.
21 “Jèhófà bínú sí mi torí yín,+ ó sì búra pé mi ò ní sọdá Jọ́dánì, mi ò sì ní wọ ilẹ̀ dáradára tí Jèhófà Ọlọ́run yín fẹ́ fún yín láti jogún.+ 22 Ilẹ̀ yìí ni màá kú sí; mi ò ní sọdá Jọ́dánì,+ ṣùgbọ́n ẹ̀yin máa sọdá, ẹ sì máa gba ilẹ̀ dáradára náà. 23 Ẹ ṣọ́ra kí ẹ má bàa gbàgbé májẹ̀mú tí Jèhófà Ọlọ́run yín bá yín dá,+ ẹ má sì gbẹ́ ère fún ara yín, ohun tó rí bí ohunkóhun tí Jèhófà Ọlọ́run yín kà léèwọ̀ fún yín.+ 24 Torí iná tó ń jóni run ni Jèhófà Ọlọ́run yín,+ Ọlọ́run tó fẹ́ kí ẹ máa jọ́sìn òun nìkan ṣoṣo.+
25 “Tí ẹ bá bí àwọn ọmọ, tí ẹ sì ní àwọn ọmọ ọmọ, tí ẹ sì ti pẹ́ ní ilẹ̀ náà, àmọ́ tí ẹ wá ṣe ohun tó lè fa ìparun, tí ẹ gbẹ́ ère+ èyíkéyìí, tí ẹ sì ṣe ohun tó burú lójú Jèhófà Ọlọ́run yín láti mú un bínú,+ 26 mo fi ọ̀run àti ayé ṣe ẹlẹ́rìí ta kò yín lónìí, pé ó dájú pé kíákíá lẹ máa pa run ní ilẹ̀ tí ẹ̀ ń sọdá Jọ́dánì láti lọ gbà. Ẹ ò ní pẹ́ níbẹ̀, ṣe lẹ máa pa run pátápátá.+ 27 Jèhófà máa tú yín ká sáàárín àwọn èèyàn,+ díẹ̀ nínú yín ló sì máa ṣẹ́ kù+ láàárín àwọn orílẹ̀-èdè tí Jèhófà máa lé yín lọ. 28 Àwọn ọlọ́run tí wọ́n fi igi àti òkúta ṣe lẹ máa sìn níbẹ̀, èyí tí àwọn èèyàn fi ọwọ́ ṣe,+ àwọn ọlọ́run tí kò lè ríran, tí kò lè gbọ́ràn, tí kò lè jẹun, tí kò sì lè gbóòórùn.
29 “Tí ẹ bá wá Jèhófà Ọlọ́run yín níbẹ̀, ó dájú pé ẹ máa rí i+ tí ẹ bá fi gbogbo ọkàn yín àti gbogbo ara* yín wá a.+ 30 Tí wàhálà tó le gan-an bá dé bá ọ, tí gbogbo nǹkan yìí sì wá ṣẹlẹ̀ sí ọ, wàá pa dà sọ́dọ̀ Jèhófà Ọlọ́run rẹ, wàá sì fetí sí ohùn rẹ̀.+ 31 Torí Ọlọ́run aláàánú ni Jèhófà Ọlọ́run rẹ.+ Kò ní pa ọ́ tì, kò ní pa ọ́ run, kò sì ní gbàgbé májẹ̀mú tó bá àwọn baba ńlá rẹ dá.+
32 “Béèrè báyìí nípa ìgbà àtijọ́, ṣáájú ìgbà tìẹ, láti ọjọ́ tí Ọlọ́run ti dá èèyàn sí ayé; wádìí láti ìpẹ̀kun kan ọ̀run sí ìpẹ̀kun kejì. Ṣé irú nǹkan àgbàyanu bẹ́ẹ̀ ti ṣẹlẹ̀ rí àbí ẹ ti gbọ́ ohunkóhun tó jọ ọ́ rí?+ 33 Ǹjẹ́ àwọn èèyàn míì gbọ́ ohùn Ọlọ́run tó ń sọ̀rọ̀ látinú iná bí ẹ ṣe gbọ́ ọ, tí ẹ ò sì kú?+ 34 Àbí Ọlọ́run ti gbìyànjú láti mú orílẹ̀-èdè kan fún ara rẹ̀ látinú orílẹ̀-èdè míì pẹ̀lú àwọn ìdájọ́,* àmì, iṣẹ́ ìyanu,+ ogun,+ pẹ̀lú ọwọ́ agbára,+ apá tó nà jáde, tó sì ṣe àwọn nǹkan tó ń bani lẹ́rù,+ bí Jèhófà Ọlọ́run yín ṣe ṣe fún yín ní Íjíbítì níṣojú yín? 35 Ẹ̀yin fúnra yín ti rí nǹkan wọ̀nyí kí ẹ lè mọ̀ pé Jèhófà ni Ọlọ́run tòótọ́;+ kò sí ẹlòmíì àfi òun nìkan.+ 36 Ó mú kí o gbọ́ ohùn rẹ̀ láti ọ̀run, kó lè tọ́ ọ sọ́nà, ó mú kí o rí iná ńlá rẹ̀ ní ayé, o sì gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀ látinú iná.+
37 “Torí pé ó nífẹ̀ẹ́ àwọn baba ńlá rẹ, ó sì yan àtọmọdọ́mọ* wọn lẹ́yìn wọn,+ ó fi agbára ńlá rẹ̀ mú ọ kúrò ní Íjíbítì pẹ̀lú ojú rẹ̀ lára rẹ. 38 Ó lé àwọn orílẹ̀-èdè tó tóbi, tí wọ́n sì lágbára jù ọ́ lọ kúrò níwájú rẹ, kó lè mú ọ wọlé, kó sì fún ọ ní ilẹ̀ wọn kí o lè jogún rẹ̀, bó ṣe rí lónìí.+ 39 Torí náà, kí o mọ̀ lónìí, kí o sì fi sọ́kàn pé Jèhófà ni Ọlọ́run tòótọ́ lókè ọ̀run àti lórí ilẹ̀ ayé.+ Kò sí ẹlòmíì.+ 40 Kí o máa tẹ̀ lé àwọn ìlànà àti àwọn àṣẹ rẹ̀, èyí tí mò ń pa láṣẹ fún ọ lónìí, kí nǹkan lè máa lọ dáadáa fún ìwọ àti àwọn ọmọ rẹ lẹ́yìn rẹ, kí o lè pẹ́ lórí ilẹ̀ tí Jèhófà Ọlọ́run rẹ máa fún ọ.”+
41 Nígbà yẹn, Mósè ya ìlú mẹ́ta sọ́tọ̀ ní apá ìlà oòrùn Jọ́dánì.+ 42 Tí apààyàn èyíkéyìí bá ṣèèṣì pa ọmọnìkejì rẹ̀, tí kì í sì í ṣe pé ó kórìíra rẹ̀ tẹ́lẹ̀,+ kó sá lọ sí ọ̀kan lára àwọn ìlú yìí, kí wọ́n má bàa pa á.+ 43 Àwọn ìlú náà ni Bésérì+ ní aginjù, lórí ilẹ̀ tó tẹ́jú,* fún àwọn ọmọ Rúbẹ́nì, Rámótì+ ní Gílíádì fún àwọn ọmọ Gádì àti Gólánì+ ní Báṣánì fún àwọn ọmọ Mánásè.+
44 Èyí ni Òfin+ tí Mósè fi lélẹ̀ níwájú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì. 45 Èyí ni àwọn ìrántí, àwọn ìlànà àti àwọn ìdájọ́ tí Mósè fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lẹ́yìn tí wọ́n kúrò ní Íjíbítì,+ 46 ní agbègbè Jọ́dánì, ní àfonífojì tó dojú kọ Bẹti-péórì,+ ní ilẹ̀ Síhónì ọba àwọn Ámórì, tó ń gbé ní Hẹ́ṣíbónì,+ ẹni tí Mósè àti àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣẹ́gun lẹ́yìn tí wọ́n kúrò ní Íjíbítì.+ 47 Wọ́n sì gba ilẹ̀ rẹ̀ àti ilẹ̀ Ógù+ ọba Báṣánì, àwọn ọba Ámórì méjèèjì, tí wọ́n wà ní agbègbè tó wà ní ìlà oòrùn Jọ́dánì, 48 láti Áróérì,+ èyí tó wà létí Àfonífojì Áánónì, títí dé Òkè Síónì, ìyẹn Hámónì,+ 49 àti gbogbo Árábà, ní agbègbè tó wà ní ìlà oòrùn Jọ́dánì, títí lọ dé Òkun Árábà,* ní ìsàlẹ̀ àwọn gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ Písígà.+
5 Mósè wá pe gbogbo ọmọ Ísírẹ́lì jọ, ó sì sọ fún wọn pé: “Ẹ̀yin ọmọ Ísírẹ́lì, ẹ gbọ́ àwọn ìlànà àti àwọn ìdájọ́ tí mò ń kéde fún yín lónìí, kí ẹ mọ̀ wọ́n, kí ẹ sì rí i pé ẹ̀ ń pa wọ́n mọ́. 2 Jèhófà Ọlọ́run wa bá wa dá májẹ̀mú kan ní Hórébù.+ 3 Àwọn baba ńlá wa kọ́ ni Jèhófà bá dá májẹ̀mú yìí, àwa ni, gbogbo àwa tí a wà láàyè níbí lónìí. 4 Ojúkojú ni Jèhófà bá yín sọ̀rọ̀ ní òkè náà látinú iná.+ 5 Mo dúró láàárín Jèhófà àti ẹ̀yin nígbà yẹn+ kí n lè sọ ọ̀rọ̀ Jèhófà fún yín, torí iná náà ń dẹ́rù bà yín, ẹ ò sì lè gun òkè náà lọ.+ Ó sọ pé:
6 “‘Èmi ni Jèhófà Ọlọ́run rẹ, ẹni tó mú ọ kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì, kúrò ní ilé ẹrú.+ 7 O ò gbọ́dọ̀ ní ọlọ́run kankan yàtọ̀ sí mi.*+
8 “‘O ò gbọ́dọ̀ gbẹ́ ère kankan fún ara rẹ+ tàbí kí o ṣe ohun* kan tó dà bí ohunkóhun lókè ọ̀run tàbí ní ayé tàbí nínú omi nísàlẹ̀. 9 O ò gbọ́dọ̀ forí balẹ̀ fún wọn tàbí kí o jẹ́ kí wọ́n sún ọ láti sìn wọ́n,+ torí èmi Jèhófà Ọlọ́run rẹ jẹ́ Ọlọ́run tó fẹ́ kí o máa sin òun nìkan ṣoṣo,+ tó ń fi ìyà ẹ̀ṣẹ̀ àwọn bàbá jẹ àwọn ọmọ, dórí ìran kẹta àti ìran kẹrin àwọn tó kórìíra mi,+ 10 àmọ́ tó ń fi ìfẹ́ tí kì í yẹ̀* hàn sí àwọn tó nífẹ̀ẹ́ mi títí dé ẹgbẹ̀rún ìran wọn, tí wọ́n sì ń pa àwọn àṣẹ mi mọ́.
11 “‘O ò gbọ́dọ̀ lo orúkọ Jèhófà Ọlọ́run rẹ lọ́nà tí kò tọ́,+ torí Jèhófà kò ní ṣàìfi ìyà jẹ ẹnikẹ́ni tó bá lo orúkọ rẹ̀ lọ́nà tí kò tọ́.+
12 “‘Máa pa ọjọ́ Sábáàtì mọ́, kí o lè yà á sí mímọ́, bí Jèhófà Ọlọ́run rẹ ṣe pa á láṣẹ fún ọ gẹ́lẹ́.+ 13 Ọjọ́ mẹ́fà ni kí o fi ṣiṣẹ́, kí o sì fi ṣe gbogbo iṣẹ́ rẹ,+ 14 àmọ́ ọjọ́ keje jẹ́ sábáàtì fún Jèhófà Ọlọ́run rẹ.+ O ò gbọ́dọ̀ ṣiṣẹ́ kankan,+ ìwọ àti ọmọkùnrin rẹ àti ọmọbìnrin rẹ àti ẹrúkùnrin rẹ àti ẹrúbìnrin rẹ àti akọ màlúù rẹ àti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ àti èyíkéyìí nínú ẹran ọ̀sìn rẹ àti àjèjì tó ń gbé nínú àwọn ìlú* rẹ,+ kí ẹrúkùnrin rẹ àti ẹrúbìnrin rẹ lè sinmi bíi tìẹ.+ 15 Rántí pé o di ẹrú ní ilẹ̀ Íjíbítì àti pé Jèhófà Ọlọ́run rẹ fi ọwọ́ agbára àti apá rẹ̀ tó nà jáde mú ọ kúrò níbẹ̀.+ Ìdí nìyẹn tí Jèhófà Ọlọ́run rẹ fi pàṣẹ fún ọ pé kí o máa pa ọjọ́ Sábáàtì mọ́.
16 “‘Bọlá fún bàbá rẹ àti ìyá rẹ,+ bí Jèhófà Ọlọ́run rẹ ṣe pa á láṣẹ fún ọ gẹ́lẹ́, kí ẹ̀mí rẹ lè gùn, kí nǹkan sì lè máa lọ dáadáa fún ọ lórí ilẹ̀ tí Jèhófà Ọlọ́run rẹ máa fún ọ.+
17 “‘O ò gbọ́dọ̀ pààyàn.+
18 “‘O ò sì gbọ́dọ̀ ṣe àgbèrè.+
19 “‘O ò gbọ́dọ̀ jalè.+
20 “‘O ò sì gbọ́dọ̀ jẹ́rìí èké sí ọmọnìkejì rẹ.+
21 “‘O ò gbọ́dọ̀ jẹ́ kí ìyàwó ọmọnìkejì rẹ wọ̀ ọ́ lójú.+ O ò sì gbọ́dọ̀ ṣe ojúkòkòrò ilé ọmọnìkejì rẹ tàbí oko rẹ̀ tàbí ẹrúkùnrin rẹ̀ tàbí ẹrúbìnrin rẹ̀ tàbí akọ màlúù rẹ̀ tàbí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀ tàbí ohunkóhun tó jẹ́ ti ọmọnìkejì rẹ.’+
22 “Àwọn àṣẹ* yìí ni Jèhófà pa fún gbogbo ìjọ yín lórí òkè náà, látinú iná àti ìkùukùu* àti ìṣúdùdù tó kàmàmà+ pẹ̀lú ohùn tó dún ketekete, kò sì fi ohunkóhun kún un; ó wá kọ wọ́n sórí wàláà òkúta méjì, ó sì kó o fún mi.+
23 “Àmọ́ gbàrà tí ẹ gbọ́ ohùn tó ń tinú òkùnkùn náà jáde, nígbà tí iná ń jó ní òkè náà,+ gbogbo olórí ẹ̀yà yín àti àwọn àgbààgbà wá sọ́dọ̀ mi. 24 Ẹ wá sọ pé, ‘Jèhófà Ọlọ́run wa ti fi ògo rẹ̀ àti títóbi rẹ̀ hàn wá, a sì ti gbọ́ ohùn rẹ̀ látinú iná.+ Òní la rí i pé Ọlọ́run lè bá èèyàn sọ̀rọ̀ kí onítọ̀hún má sì kú.+ 25 Ṣé ó wá yẹ ká kú ni? Iná ńlá yìí lè jó wa run. Tí a bá ṣì ń gbọ́ ohùn Jèhófà Ọlọ́run wa, ó dájú pé a máa kú. 26 Nínú gbogbo aráyé,* ta ló tíì gbọ́ ohùn Ọlọ́run alààyè tó ń sọ̀rọ̀ látinú iná bí a ṣe gbọ́ ọ, tí onítọ̀hún ò sì kú? 27 Ìwọ fúnra rẹ ni kí o sún mọ́ ibẹ̀, kí o lè gbọ́ gbogbo ohun tí Jèhófà Ọlọ́run wa máa sọ, ìwọ lo sì máa sọ gbogbo ohun tí Jèhófà Ọlọ́run wa bá bá ọ sọ fún wa, a máa gbọ́, a sì máa ṣe é.’+
28 “Jèhófà gbọ́ ohun tí ẹ sọ fún mi, Jèhófà sì sọ fún mi pé, ‘Mo ti gbọ́ ohun tí àwọn èèyàn yìí sọ fún ọ. Gbogbo ohun tí wọ́n sọ ló dáa.+ 29 Ì bá mà dáa o, tí wọ́n bá mú kí ọkàn wọn máa bẹ̀rù mi nígbà gbogbo,+ tí wọ́n ń pa gbogbo àṣẹ mi mọ́,+ nǹkan á máa lọ dáadáa fún àwọn àti àwọn ọmọ wọn títí láé!+ 30 Lọ sọ fún wọn pé: “Ẹ pa dà sínú àwọn àgọ́ yín.” 31 Àmọ́ kí ìwọ dúró sọ́dọ̀ mi, kí n lè sọ gbogbo àṣẹ, ìlànà àti ìdájọ́ tí o máa kọ́ wọn fún ọ, èyí tí wọ́n á máa tẹ̀ lé ní ilẹ̀ tí màá fún wọn pé kó di tiwọn.’ 32 Kí ẹ rí i pé ohun tí Jèhófà Ọlọ́run yín pa láṣẹ fún yín gẹ́lẹ́ lẹ̀ ń ṣe.+ Ẹ ò gbọ́dọ̀ yà sí ọ̀tún tàbí sí òsì.+ 33 Gbogbo ọ̀nà tí Jèhófà Ọlọ́run yín pa láṣẹ fún yín ni kí ẹ máa rìn,+ kí ẹ lè máa wà láàyè, kí nǹkan lè máa lọ dáadáa fún yín, kí ẹ sì lè pẹ́ lórí ilẹ̀ tí ẹ máa gbà.+
6 “Èyí ni àwọn àṣẹ, ìlànà àti ìdájọ́ tí Jèhófà Ọlọ́run yín fi lélẹ̀ láti kọ́ yín, kí ẹ lè máa pa wọ́n mọ́ tí ẹ bá ti sọdá sí ilẹ̀ tí ẹ máa gbà, 2 kí ẹ lè máa bẹ̀rù Jèhófà Ọlọ́run yín, kí ẹ sì máa pa gbogbo òfin àti àṣẹ rẹ̀ tí mò ń pa láṣẹ fún yín mọ́, ẹ̀yin àti ọmọ yín àti ọmọ ọmọ yín,+ ní gbogbo ọjọ́ ayé yín, kí ẹ̀mí yín lè gùn.+ 3 Kí o fetí sílẹ̀, ìwọ Ísírẹ́lì, kí o sì rí i pé ò ń pa wọ́n mọ́, kí nǹkan lè máa lọ dáadáa fún ọ, kí o sì lè pọ̀ rẹpẹtẹ ní ilẹ̀ tí wàrà àti oyin ti ń ṣàn, bí Jèhófà Ọlọ́run àwọn baba ńlá rẹ ṣe ṣèlérí fún ọ gẹ́lẹ́.
4 “Fetí sílẹ̀, ìwọ Ísírẹ́lì: Jèhófà Ọlọ́run wa, Jèhófà kan ṣoṣo ni.+ 5 Kí o fi gbogbo ọkàn rẹ àti gbogbo ara* rẹ+ àti gbogbo okun rẹ*+ nífẹ̀ẹ́ Jèhófà Ọlọ́run rẹ. 6 Rí i pé o fi àwọn ọ̀rọ̀ yìí tí mò ń pa láṣẹ fún ọ lónìí sọ́kàn, 7 kí o máa fi kọ́ àwọn ọmọ rẹ+ léraléra,* kí o sì máa sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ nígbà tí o bá jókòó nínú ilé rẹ, nígbà tí o bá ń rìn lójú ọ̀nà, nígbà tí o bá dùbúlẹ̀ àti nígbà tí o bá dìde.+ 8 So ó mọ́ ọwọ́ rẹ bí ohun ìrántí, kó sì dà bí aṣọ ìwérí níwájú orí rẹ.*+ 9 Kọ ọ́ sára àwọn òpó ilẹ̀kùn ilé rẹ àti sí àwọn ẹnubodè rẹ.
10 “Tí Jèhófà Ọlọ́run rẹ bá mú ọ dé ilẹ̀ tó búra fún àwọn baba ńlá rẹ Ábúráhámù, Ísákì àti Jékọ́bù pé òun máa fún ọ,+ àwọn ìlú tó tóbi tó sì dára, tí kì í ṣe ìwọ lo kọ́ ọ,+ 11 àwọn ilé tí gbogbo onírúurú ohun rere tí ìwọ kò ṣiṣẹ́ fún kún inú wọn, àwọn kòtò omi tí ìwọ kò gbẹ́, àwọn ọgbà àjàrà àti igi ólífì tí ìwọ kò gbìn, tí o jẹ, tí o sì yó,+ 12 rí i pé o ò gbàgbé Jèhófà,+ ẹni tó mú ọ kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì, kúrò ní ilé ẹrú. 13 Jèhófà Ọlọ́run rẹ ni kí o máa bẹ̀rù,+ òun ni kí o máa sìn,+ orúkọ rẹ̀ sì ni kí o máa fi búra.+ 14 Ẹ ò gbọ́dọ̀ tẹ̀ lé àwọn ọlọ́run míì, èyíkéyìí nínú ọlọ́run àwọn èèyàn tó yí yín ká,+ 15 torí Ọlọ́run tó fẹ́ kí á máa sin òun nìkan ṣoṣo ni Jèhófà Ọlọ́run rẹ+ tó wà láàárín rẹ. Àìjẹ́ bẹ́ẹ̀, Jèhófà máa bínú sí ọ gidigidi,+ yóò sì pa ọ́ run kúrò lórí ilẹ̀.+
16 “Ẹ ò gbọ́dọ̀ dán Jèhófà Ọlọ́run yín wò,+ bí ẹ ṣe dán an wò ní Másà.+ 17 Kí ẹ rí i pé ẹ̀ ń pa àwọn àṣẹ Jèhófà Ọlọ́run yín mọ́ délẹ̀délẹ̀ àti àwọn ìránnilétí rẹ̀ àti àwọn ìlànà rẹ̀, tó pa láṣẹ pé kí ẹ máa tẹ̀ lé. 18 Kí o máa ṣe ohun tó tọ́, tó sì dáa ní ojú Jèhófà, kí nǹkan lè máa lọ dáadáa fún ọ, kí o lè wọ ilẹ̀ dáradára tí Jèhófà búra fún àwọn baba ńlá rẹ nípa rẹ̀, kí o sì gbà á,+ 19 nígbà tí o bá lé gbogbo ọ̀tá rẹ kúrò níwájú rẹ, bí Jèhófà ṣe ṣèlérí.+
20 “Lọ́jọ́ iwájú, tí ọmọ rẹ bá bi ọ́ pé, ‘Kí ni ìtumọ̀ àwọn ìránnilétí, àwọn ìlànà àti àwọn ìdájọ́ tí Jèhófà Ọlọ́run wa pa láṣẹ fún yín?’ 21 kí o sọ fún ọmọ rẹ pé, ‘A di ẹrú Fáráò ní Íjíbítì, àmọ́ Jèhófà fi ọwọ́ agbára mú wa jáde ní Íjíbítì. 22 Ojú wa ni Jèhófà ṣe ń fi àwọn iṣẹ́ àmì àti iṣẹ́ ìyanu tó lágbára tó sì ń ṣọṣẹ́ kọ lu Íjíbítì,+ Fáráò àti gbogbo agbo ilé rẹ̀.+ 23 Ó sì mú wa kúrò níbẹ̀, kó lè mú wa wá síbí láti fún wa ní ilẹ̀ tó búra fún àwọn baba ńlá wa nípa rẹ̀.+ 24 Jèhófà wá pàṣẹ fún wa pé ká máa tẹ̀ lé gbogbo ìlànà yìí, ká sì máa bẹ̀rù Jèhófà Ọlọ́run wa fún àǹfààní ara wa títí lọ,+ ká lè máa wà láàyè+ bí a ṣe wà láàyè títí dòní. 25 A ó sì kà wá sí olódodo tí a bá rí i pé gbogbo àṣẹ yìí là ń pa mọ́ láti fi hàn pé à ń ṣègbọràn sí* Jèhófà Ọlọ́run wa, bó ṣe pa á láṣẹ fún wa.’+
7 “Tí Jèhófà Ọlọ́run rẹ bá mú ọ dé ilẹ̀ tí o fẹ́ wọ̀ tí o sì máa gbà,+ ó máa mú àwọn orílẹ̀-èdè tí èèyàn wọn pọ̀ kúrò níwájú rẹ:+ àwọn ọmọ Hétì, àwọn Gẹ́gáṣì, àwọn Ámórì,+ àwọn ọmọ Kénáánì, àwọn Pérísì, àwọn Hífì àti àwọn ará Jébúsì,+ àwọn orílẹ̀-èdè méje tí èèyàn wọn pọ̀ tí wọ́n sì lágbára jù ọ́ lọ.+ 2 Jèhófà Ọlọ́run rẹ máa fi wọ́n lé ọ lọ́wọ́, wàá sì ṣẹ́gun wọn.+ Kí o rí i pé o pa wọ́n run pátápátá.+ O ò gbọ́dọ̀ bá wọn dá májẹ̀mú kankan, o ò sì gbọ́dọ̀ ṣojúure sí wọn rárá.+ 3 O ò gbọ́dọ̀ bá wọn dána rárá.* O ò gbọ́dọ̀ fi àwọn ọmọbìnrin rẹ fún àwọn ọmọkùnrin wọn, o ò sì gbọ́dọ̀ fẹ́ àwọn ọmọbìnrin wọn fún àwọn ọmọkùnrin rẹ.+ 4 Torí wọn ò ní jẹ́ kí àwọn ọmọkùnrin rẹ tọ̀ mí lẹ́yìn mọ́, wọ́n á mú kí wọ́n máa sin àwọn ọlọ́run míì;+ Jèhófà máa wá bínú gidigidi sí ọ, kíákíá ló sì máa pa ọ́ run.+
5 “Kàkà bẹ́ẹ̀, ohun tí ẹ máa ṣe sí wọn nìyí: Ẹ wó àwọn pẹpẹ wọn lulẹ̀, ẹ sì wó àwọn ọwọ̀n òrìṣà wọn,+ ẹ gé àwọn òpó òrìṣà* wọn,+ kí ẹ sì dáná sun àwọn ère gbígbẹ́ wọn.+ 6 Torí èèyàn mímọ́ lẹ jẹ́ fún Jèhófà Ọlọ́run yín, Jèhófà Ọlọ́run yín sì ti yàn yín kí ẹ lè di èèyàn rẹ̀, ohun ìní rẹ̀ pàtàkì,* nínú gbogbo èèyàn tó wà láyé.+
7 “Kì í ṣe torí pé ẹ̀yin lẹ pọ̀ jù nínú gbogbo èèyàn ni Jèhófà ṣe nífẹ̀ẹ́ yín tó sì yàn yín,+ ẹ̀yin lẹ kéré jù nínú gbogbo èèyàn.+ 8 Àmọ́ torí pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ yín, tó sì ṣe ohun tó búra fún àwọn baba ńlá yín+ pé òun máa ṣe ni Jèhófà ṣe fi ọwọ́ agbára mú yín kúrò, kó lè rà yín pa dà kúrò ní ilé ẹrú,+ kúrò lọ́wọ́* Fáráò ọba Íjíbítì. 9 O mọ̀ dáadáa pé Jèhófà Ọlọ́run rẹ ni Ọlọ́run tòótọ́, Ọlọ́run tó ṣeé fọkàn tán, tó ń pa májẹ̀mú rẹ̀ mọ́, tó sì ń fi ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ hàn títí dé ẹgbẹ̀rún ìran àwọn tó nífẹ̀ẹ́ rẹ̀, tí wọ́n sì ń pa àwọn àṣẹ rẹ̀ mọ́.+ 10 Àmọ́ ó máa fi ìparun san ẹ̀san fún àwọn tó kórìíra rẹ̀ ní tààràtà.+ Kò ní jáfara láti fìyà jẹ àwọn tó kórìíra rẹ̀; ó máa san wọ́n lẹ́san lójúkojú. 11 Torí náà, rí i pé o pa àwọn àṣẹ àti àwọn ìlànà àti àwọn ìdájọ́ tí mò ń pa láṣẹ fún ọ lónìí mọ́, kí o máa tẹ̀ lé wọn.
12 “Tí ẹ bá ń tẹ́tí sí àwọn ìdájọ́ yìí, tí ẹ̀ ń tẹ̀ lé wọn, tí ẹ sì ń pa wọ́n mọ́, Jèhófà Ọlọ́run yín máa pa májẹ̀mú tó bá àwọn baba ńlá yín dá mọ́, ó sì máa fi ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ hàn bó ṣe ṣèlérí. 13 Ó máa nífẹ̀ẹ́ rẹ, ó máa bù kún ọ, ó sì máa sọ ọ́ di púpọ̀. Àní, ó máa fi ọmọ púpọ̀ bù kún ọ,*+ ó máa fi èso ilẹ̀ rẹ bù kún ọ, ó sì máa fi ọkà rẹ, wáìnì tuntun rẹ, òróró rẹ,+ àwọn ọmọ màlúù nínú ọ̀wọ́ ẹran rẹ àti àwọn ọ̀dọ́ àgùntàn nínú agbo ẹran rẹ bù kún ọ ní ilẹ̀ tó búra fún àwọn baba ńlá rẹ pé òun máa fún ọ.+ 14 Ìwọ lo máa gba ìbùkún jù nínú gbogbo èèyàn;+ kò ní sí ọkùnrin tàbí obìnrin kankan láàárín rẹ tí kò ní bímọ, ẹran ọ̀sìn rẹ ò sì ní wà láìbímọ.+ 15 Jèhófà máa mú gbogbo àìsàn kúrò lára rẹ; kò sì ní jẹ́ kí ìkankan nínú gbogbo àrùn burúkú tí o ti mọ̀ ní Íjíbítì ṣe ọ́.+ Kàkà bẹ́ẹ̀, gbogbo àwọn tó kórìíra rẹ ló máa fi àrùn náà ṣe. 16 Kí o run gbogbo èèyàn tí Jèhófà Ọlọ́run rẹ bá fi lé ọ lọ́wọ́.+ O* ò gbọ́dọ̀ káàánú wọn,+ o ò sì gbọ́dọ̀ sin àwọn ọlọ́run wọn,+ torí ìdẹkùn ló máa jẹ́ fún ọ.+
17 “Tí o bá sọ ní ọkàn rẹ pé, ‘Àwọn orílẹ̀-èdè yìí pọ̀ jù wá lọ. Báwo ni màá ṣe lé wọn lọ?’+ 18 o ò gbọ́dọ̀ bẹ̀rù wọn.+ Rán ara rẹ létí ohun tí Jèhófà Ọlọ́run rẹ ṣe sí Fáráò àti gbogbo Íjíbítì,+ 19 àwọn ìdájọ́* tó rinlẹ̀ tí o fojú ara rẹ rí, àwọn iṣẹ́ àmì àti àwọn iṣẹ́ ìyanu+ àti ọwọ́ agbára àti apá tí Jèhófà Ọlọ́run rẹ nà jáde tó fi mú ọ kúrò.+ Ohun tí Jèhófà Ọlọ́run rẹ máa ṣe sí gbogbo àwọn tí ò ń bẹ̀rù nìyẹn.+ 20 Jèhófà Ọlọ́run rẹ máa mú kí wọ́n rẹ̀wẹ̀sì* títí àwọn tó ṣẹ́ kù+ àti àwọn tó ń fara pa mọ́ fún ọ fi máa pa run. 21 Má gbọ̀n rìrì nítorí wọn, torí Jèhófà Ọlọ́run rẹ wà pẹ̀lú rẹ,+ Ọlọ́run tó tóbi ni, tó sì yẹ lẹ́ni tí à ń bẹ̀rù.+
22 “Ó dájú pé díẹ̀díẹ̀ ni Jèhófà Ọlọ́run rẹ máa lé àwọn orílẹ̀-èdè yìí kúrò níwájú rẹ.+ Kò ní jẹ́ kí o pa wọ́n run kíákíá, kí àwọn ẹranko búburú má bàa pọ̀ níbẹ̀ kí wọ́n sì ṣe yín lọ́ṣẹ́. 23 Jèhófà Ọlọ́run rẹ máa fi wọ́n lé ọ lọ́wọ́ títí o fi máa ṣẹ́gun wọn tí o sì máa pa wọ́n run pátápátá.+ 24 Ó máa fi àwọn ọba wọn lé ọ lọ́wọ́,+ o sì máa pa orúkọ wọn run kúrò lábẹ́ ọ̀run.+ Kò sẹ́ni tó máa dìde sí ọ+ títí o fi máa pa wọ́n run tán.+ 25 Kí ẹ dáná sun ère àwọn ọlọ́run wọn tí wọ́n gbẹ́.+ Má ṣe jẹ́ kí ojú rẹ wọ fàdákà àti wúrà tó wà lára wọn, o ò sì gbọ́dọ̀ mú un fún ara rẹ,+ kó má bàa jẹ́ ìdẹkùn fún ọ, torí ohun ìríra ló jẹ́ lójú Jèhófà Ọlọ́run rẹ.+ 26 O ò gbọ́dọ̀ mú ohun ìríra wọnú ilé rẹ, kí o má bàa di ohun tí a máa pa run bí ohun ìríra náà. Kí o kà á sí ẹ̀gbin, kí o sì kórìíra rẹ̀ pátápátá, torí ohun tí a máa pa run ni.
8 “Ẹ rí i pé ẹ̀ ń tẹ̀ lé gbogbo àṣẹ tí mò ń pa fún yín lónìí, kí ẹ lè máa wà láàyè,+ kí ẹ máa pọ̀ sí i, kí ẹ sì wọ ilẹ̀ tí Jèhófà búra nípa rẹ̀ fún àwọn baba ńlá yín kí ẹ lè gbà á.+ 2 Máa rántí ọ̀nà jíjìn tí Jèhófà Ọlọ́run rẹ mú ọ rìn ní aginjù fún ogójì (40) ọdún yìí,+ kó lè rẹ̀ ọ́ sílẹ̀, kó sì dán ọ wò,+ kó lè mọ ohun tó wà lọ́kàn rẹ,+ bóyá wàá pa àwọn àṣẹ rẹ̀ mọ́ tàbí o ò ní pa wọ́n mọ́. 3 Torí náà, ó rẹ̀ ọ́ sílẹ̀, ó jẹ́ kí ebi pa ọ́,+ ó sì fi mánà bọ́ ọ,+ oúnjẹ tí o kò mọ̀, tí àwọn bàbá rẹ ò sì mọ̀, kí o lè mọ̀ pé kì í ṣe oúnjẹ nìkan ṣoṣo ló ń mú kí èèyàn wà láàyè, àmọ́ gbogbo ọ̀rọ̀ tó ń ti ẹnu Jèhófà jáde ni èèyàn fi ń wà láàyè.+ 4 Aṣọ tí o wọ̀ ò gbó, ẹsẹ̀ rẹ ò sì wú jálẹ̀ ogójì (40) ọdún yìí.+ 5 O mọ̀ dáadáa lọ́kàn rẹ pé bí bàbá ṣe ń tọ́ ọmọ rẹ̀ sọ́nà ni Jèhófà Ọlọ́run rẹ ń tọ́ ọ sọ́nà.+
6 “Torí náà, o gbọ́dọ̀ máa pa àwọn àṣẹ Jèhófà Ọlọ́run rẹ mọ́, nípa rírìn ní àwọn ọ̀nà rẹ̀, kí o sì máa bẹ̀rù rẹ̀. 7 Torí ilẹ̀ dáradára ni Jèhófà Ọlọ́run rẹ ń mú ọ lọ,+ ilẹ̀ tí omi ti ń ṣàn,* tí omi ti ń sun jáde, tí omi sì ti ń tú jáde* ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ àti ní agbègbè olókè, 8 ilẹ̀ tí àlìkámà* àti ọkà bálì kún inú rẹ̀ pẹ̀lú àwọn igi àjàrà, igi ọ̀pọ̀tọ́ àti pómégíránétì,+ ilẹ̀ tí òróró ólífì àti oyin kún inú rẹ̀,+ 9 ilẹ̀ tí oúnjẹ ò ti ní wọ́n ọ, tó ò sì ní ṣaláìní ohunkóhun, ilẹ̀ tí irin wà nínú àwọn òkúta rẹ̀, tí wàá sì máa wa bàbà látinú àwọn òkè rẹ̀.
10 “Tí o bá ti jẹun, tí o sì ti yó, kí o yin Jèhófà Ọlọ́run rẹ lógo torí ilẹ̀ dáradára tó fún ọ.+ 11 Kí o má bàa gbàgbé Jèhófà Ọlọ́run rẹ, rí i pé o pa àwọn òfin rẹ̀, ìdájọ́ rẹ̀ àti àwọn àṣẹ rẹ̀ mọ́, èyí tí mò ń pa láṣẹ fún ọ lónìí. 12 Tí o bá ti jẹun, tí o sì ti yó, tí o ti kọ́ àwọn ilé tó rẹwà, tí o sì ń gbé níbẹ̀,+ 13 tí ọ̀wọ́ ẹran rẹ àti agbo ẹran rẹ di púpọ̀, tí fàdákà àti wúrà rẹ pọ̀ sí i, tí gbogbo ohun ìní rẹ sì pọ̀ rẹpẹtẹ, 14 má ṣe gbéra ga nínú ọkàn rẹ,+ kó sì mú kí o gbàgbé Jèhófà Ọlọ́run rẹ tó mú ọ kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì, kúrò ní ilé ẹrú,+ 15 ẹni tó mú ọ rin inú aginjù tí ó tóbi tó sì ń bani lẹ́rù,+ tó ní àwọn ejò olóró àti àwọn àkekèé, tí ilẹ̀ ibẹ̀ gbẹ tí kò sì lómi. Ó mú kí omi ṣàn jáde látinú akọ àpáta,+ 16 ó sì fi mánà bọ́ ọ+ nínú aginjù, èyí tí àwọn bàbá rẹ ò mọ̀, kó lè rẹ̀ ọ́ sílẹ̀,+ kó sì dán ọ wò, kó lè ṣe ọ́ láǹfààní lọ́jọ́ ọ̀la.+ 17 Tí o bá sọ lọ́kàn rẹ pé, ‘Agbára mi àti iṣẹ́ ọwọ́ mi ló sọ mí di ọlọ́rọ̀,’+ 18 rántí pé Jèhófà Ọlọ́run rẹ ló fún ọ lágbára láti di ọlọ́rọ̀,+ kó lè mú májẹ̀mú rẹ̀ tó bá àwọn baba ńlá rẹ dá ṣẹ, bó ṣe rí lónìí.+
19 “Tí ẹ bá gbàgbé Jèhófà Ọlọ́run yín pẹ́nrẹ́n, tí ẹ wá ń tọ àwọn ọlọ́run míì lẹ́yìn, tí ẹ̀ ń sìn wọ́n, tí ẹ sì ń forí balẹ̀ fún wọn, mo ta kò yín lónìí pé ó dájú pé ẹ máa pa run.+ 20 Bíi ti àwọn orílẹ̀-èdè tí Jèhófà máa pa run níwájú yín, bẹ́ẹ̀ lẹ ṣe máa pa run, torí ẹ ò fetí sí ohùn Jèhófà Ọlọ́run yín.+
9 “Gbọ́, ìwọ Ísírẹ́lì, ò ń sọdá Jọ́dánì lónìí,+ láti wọ ilẹ̀ náà kí o lè lọ lé àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n tóbi, tí wọ́n sì lágbára jù ọ́ lọ kúrò,+ àwọn ìlú tó tóbi, tí wọ́n sì mọ odi rẹ̀ kan ọ̀run,*+ 2 àwọn èèyàn tó tóbi tí wọ́n sì ga, àwọn ọmọ Ánákímù+ tí ẹ mọ̀, tí ẹ sì gbọ́ tí wọ́n sọ nípa wọn pé, ‘Ta ló lè ko àwọn ọmọ Ánákì lójú?’ 3 Torí náà, kí o mọ̀ lónìí pé Jèhófà Ọlọ́run rẹ máa sọdá ṣáájú rẹ.+ Ó jẹ́ iná tó ń jóni run,+ ó sì máa pa wọ́n run. Ó máa tẹ̀ wọ́n lórí ba níṣojú yín kí ẹ lè tètè lé wọn jáde,* kí ẹ sì pa wọ́n run, bí Jèhófà ṣe ṣèlérí fún ọ.+
4 “Tí Jèhófà Ọlọ́run rẹ bá lé wọn kúrò níwájú rẹ, má sọ lọ́kàn rẹ pé, ‘Òdodo mi ló mú kí Jèhófà mú mi wá gba ilẹ̀ yìí.’+ Torí ìwà burúkú àwọn orílẹ̀-èdè yìí+ ni Jèhófà ṣe máa lé wọn kúrò níwájú rẹ. 5 Kì í ṣe torí pé o jẹ́ olódodo tàbí olóòótọ́ nínú ọkàn rẹ ló máa jẹ́ kí o lọ gba ilẹ̀ wọn. Àmọ́ ìwà burúkú àwọn orílẹ̀-èdè yìí ló máa mú kí Jèhófà Ọlọ́run rẹ lé wọn kúrò níwájú rẹ,+ kí ọ̀rọ̀ tí Jèhófà búra nípa rẹ̀ fún àwọn baba ńlá yín, Ábúráhámù,+ Ísákì+ àti Jékọ́bù+ sì lè ṣẹ. 6 Torí náà, mọ̀ pé kì í ṣe torí òdodo rẹ ni Jèhófà Ọlọ́run rẹ ṣe máa fún ọ ní ilẹ̀ dáradára yìí kí o lè gbà á, torí alágídí* ni ọ́.+
7 “Rántí, má sì gbàgbé bí o ṣe múnú bí Jèhófà Ọlọ́run rẹ ní aginjù.+ Láti ọjọ́ tí ẹ ti kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì títí ẹ fi dé ibí yìí lẹ ti ń ṣọ̀tẹ̀ sí Jèhófà.+ 8 Kódà ní Hórébù, ẹ múnú bí Jèhófà, Jèhófà sì bínú gidigidi sí yín débi pé ó ṣe tán láti pa yín run.+ 9 Nígbà tí mo lọ sórí òkè láti gba àwọn wàláà òkúta,+ àwọn wàláà májẹ̀mú tí Jèhófà bá yín dá,+ ogójì (40) ọ̀sán àti ogójì (40) òru+ ni mo fi wà lórí òkè náà, tí mi ò jẹ, tí mi ò sì mu. 10 Jèhófà wá fún mi ní àwọn wàláà òkúta méjì tí ìka Ọlọ́run kọ̀wé sí, gbogbo ọ̀rọ̀ tí Jèhófà bá yín sọ ní òkè náà látinú iná ní ọjọ́ tí ẹ pé jọ* sì wà lára rẹ̀.+ 11 Lẹ́yìn ogójì (40) ọ̀sán àti ogójì (40) òru náà, Jèhófà fún mi ní wàláà òkúta méjì, àwọn wàláà májẹ̀mú náà, 12 Jèhófà sì sọ fún mi pé, ‘Gbéra, tètè sọ̀ kalẹ̀ kúrò níbí, torí pé àwọn èèyàn rẹ tí o mú kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì ti hùwà ìbàjẹ́.+ Wọ́n ti yára kúrò ní ọ̀nà tí mo pa láṣẹ fún wọn pé kí wọ́n máa rìn. Wọ́n ti ṣe ère onírin* fún ara wọn.’+ 13 Jèhófà wá sọ fún mi pé, ‘Mo ti rí àwọn èèyàn yìí, wò ó! alágídí* ni wọ́n.+ 14 Dá mi dá wọn, màá pa wọ́n run, màá sì pa orúkọ wọn rẹ́ lábẹ́ ọ̀run, sì jẹ́ kí n sọ ìwọ di orílẹ̀-èdè tó lágbára tó sì pọ̀ jù wọ́n lọ.’+
15 “Mo bá yíjú pa dà, mo sì sọ̀ kalẹ̀ lórí òkè náà nígbà tí iná ń jó lórí rẹ̀,+ wàláà májẹ̀mú méjì náà sì wà ní ọwọ́ mi méjèèjì.+ 16 Nígbà náà, mo rí i pé ẹ ti ṣẹ Jèhófà Ọlọ́run yín! Ẹ ti ṣe ọmọ màlúù onírin* fún ara yín. Ẹ ti yára kúrò ní ọ̀nà tí Jèhófà pa láṣẹ pé kí ẹ máa rìn.+ 17 Mo bá mú wàláà méjèèjì, mo fi ọwọ́ mi méjèèjì là á mọ́lẹ̀, mo sì fọ́ ọ túútúú níṣojú yín.+ 18 Mo wá wólẹ̀ níwájú Jèhófà, bíi ti àkọ́kọ́, fún ogójì (40) ọ̀sán àti ogójì (40) òru. Mi ò jẹ, mi ò sì mu,+ torí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ tí ẹ dá bí ẹ ṣe ṣe ohun tó burú lójú Jèhófà, tí ẹ sì ń múnú bí i. 19 Bí Jèhófà ṣe bínú sí yín gidigidi bà mí lẹ́rù gan-an,+ torí ó ṣe tán láti pa yín run. Àmọ́, Jèhófà tún fetí sí mi nígbà yẹn.+
20 “Jèhófà bínú sí Áárónì débi pé ó ṣe tán láti pa á run,+ àmọ́ mo bá Áárónì náà bẹ̀bẹ̀ nígbà yẹn. 21 Lẹ́yìn náà, mo mú ohun tí ẹ ṣe tó mú kí ẹ dẹ́ṣẹ̀, ìyẹn ọmọ màlúù náà,+ mo sì dáná sun ún; mo fọ́ ọ túútúú, mo sì lọ̀ ọ́ kúnná títí ó fi di lẹ́búlẹ́bú bí eruku, mo sì dà á sínú odò tó ń ṣàn látorí òkè náà.+
22 “Bákan náà, ẹ tún múnú bí Jèhófà ní Tábérà,+ Másà+ àti ní Kiburoti-hátááfà.+ 23 Nígbà tí Jèhófà ní kí ẹ lọ láti Kadeṣi-bánéà,+ tó sì sọ pé, ‘Ẹ gòkè lọ gba ilẹ̀ tó dájú pé màá fún yín!’ ẹ tún ṣe ohun tó lòdì sí àṣẹ tí Jèhófà Ọlọ́run yín pa,+ ẹ ò gbà á gbọ́,+ ẹ ò sì ṣègbọràn sí i. 24 Àtìgbà tí mo ti mọ̀ yín lẹ ti ń ṣọ̀tẹ̀ sí Jèhófà.
25 “Torí náà, mo fi ogójì (40) ọ̀sán àti ogójì (40) òru+ wólẹ̀ níwájú Jèhófà, mo wólẹ̀ bẹ́ẹ̀ torí Jèhófà sọ pé òun máa pa yín run. 26 Mo bẹ̀rẹ̀ sí í bẹ Jèhófà, mo sì sọ pé, ‘Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ, má pa àwọn èèyàn rẹ run. Ohun ìní* rẹ ni wọ́n jẹ́,+ àwọn tí o fi títóbi rẹ rà pa dà, tí o sì fi ọwọ́ agbára mú kúrò ní Íjíbítì.+ 27 Rántí àwọn ìránṣẹ́ rẹ Ábúráhámù, Ísákì àti Jékọ́bù.+ Má wo ti agídí àwọn èèyàn yìí àti ìwà burúkú wọn pẹ̀lú ẹ̀ṣẹ̀ wọn.+ 28 Àìjẹ́ bẹ́ẹ̀, àwọn èèyàn tó wà ní ilẹ̀ tí o ti mú wa kúrò lè máa sọ pé: “Jèhófà ò lè mú wọn dé ilẹ̀ tó ṣèlérí pé òun máa fún wọn, torí náà, ó mú wọn wá sínú aginjù kó lè pa wọ́n torí ó kórìíra wọn.”+ 29 Èèyàn rẹ ni wọ́n, ohun ìní* rẹ+ ni wọ́n sì jẹ́, àwọn tí o fi agbára ńlá rẹ àti apá rẹ tí o nà jáde mú kúrò.’+
10 “Ìgbà yẹn ni Jèhófà sọ fún mi pé, ‘Kí ìwọ fúnra rẹ gbẹ́ wàláà òkúta méjì, irú ti àkọ́kọ́,+ kí o sì wá bá mi lórí òkè náà; kí ìwọ fúnra rẹ tún fi pákó ṣe àpótí.* 2 Màá kọ àwọn ọ̀rọ̀ tó wà lórí àwọn wàláà àkọ́kọ́ tí o fọ́ túútúú sára wàláà tí o bá gbẹ́, kí o sì gbé e sínú àpótí náà.’ 3 Torí náà, mo fi igi bọn-ọ̀n-ní ṣe àpótí kan, mo sì gbẹ́ wàláà òkúta méjì, irú ti àkọ́kọ́, mo gun òkè náà lọ pẹ̀lú wàláà méjèèjì ní ọwọ́ mi.+ 4 Ó wá kọ àwọn ọ̀rọ̀ tó ti kọ tẹ́lẹ̀ sára àwọn wàláà náà,+ ìyẹn Òfin Mẹ́wàá,*+ tí Jèhófà bá yín sọ lórí òkè náà látinú iná,+ ní ọjọ́ tí ẹ pé jọ;*+ Jèhófà sì kó o fún mi. 5 Mo pa dà, mo sì sọ̀ kalẹ̀ lórí òkè náà,+ mo gbé àwọn wàláà náà sínú àpótí tí mo ṣe, wọ́n sì wà níbẹ̀, bí Jèhófà ṣe pa á láṣẹ fún mi gẹ́lẹ́.
6 “Lẹ́yìn náà, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì gbéra ní Béérótì Bene-jáákánì lọ sí Mósírà. Ibẹ̀ ni Áárónì kú sí, ibẹ̀ sì ni wọ́n sin ín sí,+ Élíásárì ọmọ rẹ̀ wá di àlùfáà dípò rẹ̀.+ 7 Wọ́n gbéra láti ibẹ̀ lọ sí Gúdígódà, láti Gúdígódà lọ sí Jótíbátà,+ ilẹ̀ tó ní àwọn odò tó ń ṣàn.*
8 “Ìgbà yẹn ni Jèhófà ya ẹ̀yà Léfì sọ́tọ̀+ kí wọ́n lè máa gbé àpótí májẹ̀mú Jèhófà,+ kí wọ́n sì máa dúró níwájú Jèhófà, kí wọ́n lè máa ṣiṣẹ́ fún un, kí wọ́n sì máa fi orúkọ rẹ̀ súre,+ bí wọ́n ṣe ń ṣe títí dòní. 9 Ìdí nìyẹn tí wọn ò fi fún Léfì ní ìpín tàbí ogún kankan pẹ̀lú àwọn arákùnrin rẹ̀. Jèhófà ni ogún rẹ̀, bí Jèhófà Ọlọ́run rẹ ṣe sọ fún un.+ 10 Èmi fúnra mi dúró sórí òkè náà bí mo ṣe ṣe nígbà àkọ́kọ́ fún ogójì (40) ọ̀sán àti ogójì (40) òru,+ Jèhófà sì tún gbọ́ mi ní àkókò yẹn.+ Jèhófà ò fẹ́ pa yín run. 11 Jèhófà wá sọ fún mi pé, ‘Máa lọ níwájú àwọn èèyàn náà, kí ẹ múra láti gbéra, kí wọ́n lè lọ gba ilẹ̀ tí mo búra fún àwọn baba ńlá wọn pé màá fún wọn.’+
12 “Ní báyìí, ìwọ Ísírẹ́lì, kí ni Jèhófà Ọlọ́run rẹ fẹ́ kí o ṣe?+ Kò ju pé: kí o máa bẹ̀rù Jèhófà Ọlọ́run rẹ,+ kí o máa rìn ní gbogbo ọ̀nà rẹ̀,+ kí o máa nífẹ̀ẹ́ rẹ̀, kí o máa fi gbogbo ọkàn rẹ àti gbogbo ara* rẹ sin Jèhófà Ọlọ́run rẹ,+ 13 kí o sì máa pa àwọn òfin àti àṣẹ Jèhófà tí mò ń pa láṣẹ fún ọ lónìí mọ́ fún àǹfààní ara rẹ.+ 14 Wò ó, Jèhófà Ọlọ́run rẹ ló ni ọ̀run, àní ọ̀run àwọn ọ̀run,* pẹ̀lú ayé àti gbogbo ohun tó wà nínú rẹ̀.+ 15 Àwọn baba ńlá yín nìkan ni Jèhófà sún mọ́ tó sì fi ìfẹ́ hàn sí, ó sì ti yan ẹ̀yin ọmọ wọn+ nínú gbogbo èèyàn, bí ẹ ṣe jẹ́ lónìí yìí. 16 Ní báyìí, kí ẹ wẹ ọkàn yín mọ́,*+ kí ẹ má sì ṣe agídí* mọ́.+ 17 Torí Jèhófà Ọlọ́run yín jẹ́ Ọlọ́run àwọn ọlọ́run+ àti Olúwa àwọn olúwa, Ọlọ́run tó tóbi, tó lágbára, tó sì yẹ lẹ́ni tí à ń bẹ̀rù, tí kì í ṣe ojúsàájú sí ẹnikẹ́ni,+ tí kì í sì í gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀. 18 Ó ń ṣe ìdájọ́ òdodo fún ọmọ aláìníbaba* àti opó,+ ó sì nífẹ̀ẹ́ àjèjì,+ ó ń fún un ní oúnjẹ àti aṣọ. 19 Kí ẹ̀yin náà nífẹ̀ẹ́ àjèjì, torí ẹ di àjèjì ní ilẹ̀ Íjíbítì.+
20 “Jèhófà Ọlọ́run rẹ ni kí o máa bẹ̀rù, òun ni kí o máa sìn,+ òun ni kí o rọ̀ mọ́, orúkọ rẹ̀ sì ni kí o máa fi búra. 21 Òun ni Ẹni tí wàá máa yìn.+ Òun ni Ọlọ́run rẹ, tó ṣe gbogbo ohun àgbàyanu àtàwọn ohun tó ń dẹ́rù bani yìí fún ọ, tí o sì fi ojú ara rẹ rí i.+ 22 Àwọn baba ńlá rẹ àti ìdílé wọn jẹ́ àádọ́rin (70) èèyàn* nígbà tí wọ́n lọ sí Íjíbítì,+ àmọ́ Jèhófà Ọlọ́run rẹ ti mú kí o pọ̀ bí ìràwọ̀ ojú ọ̀run.+
11 “Rí i pé o nífẹ̀ẹ́ Jèhófà Ọlọ́run rẹ,+ kí o máa ṣe ojúṣe rẹ sí i, kí o sì máa pa àwọn àṣẹ rẹ̀, àwọn ìdájọ́ rẹ̀ àti àwọn òfin rẹ̀ mọ́ nígbà gbogbo. 2 Ẹ mọ̀ pé ẹ̀yin ni mò ń bá sọ̀rọ̀ lónìí, kì í ṣe àwọn ọmọ yín tí wọn ò tíì mọ ìbáwí Jèhófà Ọlọ́run yín,+ títóbi rẹ̀,+ ọwọ́ agbára rẹ̀+ àti apá tó nà jáde, tí wọn ò sì tíì rí nǹkan wọ̀nyí. 3 Wọn ò rí àwọn iṣẹ́ àmì rẹ̀ àti àwọn ohun tó ṣe ní Íjíbítì sí Fáráò ọba Íjíbítì àti sí gbogbo ilẹ̀ rẹ̀;+ 4 bẹ́ẹ̀ ni wọn ò rí ohun tó ṣe sí àwọn ọmọ ogun Íjíbítì, sí àwọn ẹṣin Fáráò àti àwọn kẹ̀kẹ́ ẹṣin rẹ̀, èyí tí omi Òkun Pupa bò mọ́lẹ̀ nígbà tí wọ́n ń lé yín, tí Jèhófà sì pa wọ́n run lẹ́ẹ̀kan náà.*+ 5 Wọn ò rí ohun tó ṣe fún* yín nínú aginjù títí ẹ fi dé ibí yìí, 6 tàbí ohun tó ṣe sí Dátánì àti Ábírámù, àwọn ọmọ Élíábù ọmọ Rúbẹ́nì níṣojú gbogbo Ísírẹ́lì, nígbà tí ilẹ̀ lanu tó sì gbé wọn mì pẹ̀lú agbo ilé wọn àti àwọn àgọ́ wọn àti gbogbo ohun alààyè tó tẹ̀ lé wọn.+ 7 Ẹ ti fi ojú ara yín rí gbogbo nǹkan àgbàyanu tí Jèhófà ṣe.
8 “Kí ẹ máa pa gbogbo àṣẹ tí mò ń pa fún yín lónìí mọ́, kí ẹ lè di alágbára, kí ẹ lè kọjá sí ilẹ̀ náà, kí ẹ sì gbà á, 9 kí ẹ sì lè pẹ́ lórí ilẹ̀+ tí Jèhófà búra pé òun máa fún àwọn baba ńlá yín àti àtọmọdọ́mọ* wọn,+ ilẹ̀ tí wàrà àti oyin ti ń ṣàn.+
10 “Ilẹ̀ tí ẹ fẹ́ lọ gbà kò dà bí ilẹ̀ Íjíbítì tí ẹ ti jáde wá, níbi tí ẹ ti máa ń fún irúgbìn yín, tí ẹ sì máa ń fi ẹsẹ̀ yín bomi rin ín,* bí ọgbà tí ẹ gbin nǹkan sí. 11 Ilẹ̀ tó ní àwọn òkè àti pẹ̀tẹ́lẹ̀ ni ilẹ̀ tí ẹ fẹ́ sọdá lọ gbà.+ Òjò tó ń rọ̀ láti ọ̀run ló ń bomi rin ín;+ 12 Jèhófà Ọlọ́run yín ló ń bójú tó ilẹ̀ náà. Ojú Jèhófà Ọlọ́run yín kì í sì í kúrò ní ilẹ̀ náà, láti ìbẹ̀rẹ̀ ọdún títí di ìparí ọdún.
13 “Tí ẹ bá ń pa àwọn àṣẹ mi mọ́ délẹ̀délẹ̀, èyí tí mò ń pa fún yín lónìí, tí ẹ sì nífẹ̀ẹ́ Jèhófà Ọlọ́run yín, tí ẹ fi gbogbo ọkàn yín àti gbogbo ara* yín sìn ín,+ 14 màá mú kí òjò rọ̀ sórí ilẹ̀ yín ní àkókò rẹ̀, òjò ìgbà ìkórè àti ti ìgbà ìrúwé, ẹ sì máa kó ọkà yín jọ àti wáìnì tuntun yín àti òróró yín.+ 15 Màá mú kí ewéko hù ní oko yín fún àwọn ẹran ọ̀sìn yín, ẹ máa jẹun, ẹ sì máa yó.+ 16 Kí ẹ rí i pé ẹ ò jẹ́ kí ọkàn yín fà sí àwọn ọlọ́run míì, kí ẹ wá yà bàrá lọ sìn wọ́n tàbí kí ẹ forí balẹ̀ fún wọn.+ 17 Àìjẹ́ bẹ́ẹ̀, Jèhófà máa bínú sí yín gidigidi, ó sì máa sé ọ̀run pa kí òjò má bàa rọ̀,+ ilẹ̀ ò ní mú èso jáde, ẹ sì máa tètè pa run lórí ilẹ̀ dáradára tí Jèhófà fẹ́ fún yín.+
18 “Kí ẹ rí i pé ẹ tẹ àwọn ọ̀rọ̀ mi yìí mọ́ ọkàn yín, kó sì di ara* yín, kí ẹ so ó mọ́ ọwọ́ yín bí ohun ìrántí, kó sì dà bí aṣọ ìwérí níwájú orí yín.*+ 19 Kí ẹ fi kọ́ àwọn ọmọ yín, kí ẹ máa sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ nígbà tí ẹ bá jókòó nínú ilé yín, tí ẹ bá ń rìn lójú ọ̀nà, tí ẹ bá dùbúlẹ̀ àti nígbà tí ẹ bá dìde.+ 20 Kí ẹ kọ ọ́ sára àwọn òpó ilẹ̀kùn ilé yín àti sí àwọn ẹnubodè yín, 21 kí ẹ̀yin àti àwọn ọmọ yín lè pẹ́+ lórí ilẹ̀ tí Jèhófà búra pé òun máa fún àwọn baba ńlá yín,+ níwọ̀n ìgbà tí ayé bá ṣì wà lábẹ́ ọ̀run.
22 “Tí ẹ bá pa àṣẹ yìí tí mò ń pa fún yín mọ́ délẹ̀délẹ̀, tí ẹ sì ń tẹ̀ lé e, pé kí ẹ nífẹ̀ẹ́ Jèhófà Ọlọ́run yín,+ kí ẹ máa rìn ní gbogbo ọ̀nà rẹ̀, kí ẹ sì rọ̀ mọ́ ọn,+ 23 Jèhófà máa lé gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè yìí kúrò níwájú yín,+ ẹ sì máa lé àwọn orílẹ̀-èdè tó tóbi, tí wọ́n sì pọ̀ jù yín lọ kúrò.+ 24 Gbogbo ibi tí ẹ bá fi ẹsẹ̀ tẹ̀ ló máa di tiyín.+ Láti aginjù títí dé Lẹ́bánónì, láti Odò, ìyẹn odò Yúfírétì, dé òkun* tó wà ní ìwọ̀ oòrùn ló máa jẹ́ ààlà yín.+ 25 Ẹnì kankan ò ní dìde sí yín.+ Jèhófà Ọlọ́run yín máa kó jìnnìjìnnì bá àwọn èèyàn gbogbo ilẹ̀ tí ẹ máa tẹ̀, kí wọ́n sì máa bẹ̀rù yín,+ bó ṣe ṣèlérí fún yín gẹ́lẹ́.
26 “Wò ó, mò ń fi ìbùkún àti ègún síwájú yín lónìí:+ 27 ẹ máa rí ìbùkún tí ẹ bá ṣègbọràn sí àwọn àṣẹ Jèhófà Ọlọ́run yín tí mò ń pa fún yín lónìí,+ 28 àmọ́ ègún máa wà lórí yín bí ẹ kò bá ṣègbọràn sí àwọn àṣẹ Jèhófà Ọlọ́run yín,+ tí ẹ sì yà kúrò lójú ọ̀nà tí mò ń pa láṣẹ fún yín pé kí ẹ máa rìn lónìí, tí ẹ wá lọ ń tẹ̀ lé àwọn ọlọ́run tí ẹ ò mọ̀.
29 “Tí Jèhófà Ọlọ́run rẹ bá mú ọ dé ilẹ̀ tó máa di tìrẹ, kí o súre* ní Òkè Gérísímù, kí o sì gégùn-ún ní Òkè Ébálì.+ 30 Ṣebí òdìkejì Jọ́dánì ni wọ́n wà lápá ìwọ̀ oòrùn, ní ilẹ̀ àwọn ọmọ Kénáánì tí wọ́n ń gbé ní Árábà, ní òdìkejì Gílígálì, lẹ́gbẹ̀ẹ́ àwọn igi ńlá Mórè?+ 31 Ẹ̀ ń sọdá Jọ́dánì láti wọ ilẹ̀ tí Jèhófà Ọlọ́run yín fẹ́ fún yín, kí ẹ sì gbà á.+ Tí ẹ bá ti gbà á, tí ẹ sì wá ń gbé níbẹ̀, 32 kí ẹ rí i pé ẹ̀ ń tẹ̀ lé gbogbo ìlànà àti ìdájọ́ tí mò ń fi síwájú yín lónìí.+
12 “Èyí ni àwọn ìlànà àti àwọn ìdájọ́ tí ẹ gbọ́dọ̀ rí i pé ẹ̀ ń pa mọ́ ní gbogbo ọjọ́ tí ẹ bá fi wà láàyè lórí ilẹ̀ tí Jèhófà Ọlọ́run àwọn baba ńlá yín máa fún yín pé kó di tiyín. 2 Gbogbo ibi tí àwọn orílẹ̀-èdè tí ẹ máa lé kúrò bá ti sin àwọn ọlọ́run wọn ni kí ẹ pa run pátápátá,+ ì báà jẹ́ lórí àwọn òkè tó ga tàbí lórí àwọn òkè kéékèèké tàbí lábẹ́ igi èyíkéyìí tó gbẹ̀rẹ̀gẹ̀jigẹ̀. 3 Kí ẹ wó àwọn pẹpẹ wọn, kí ẹ fọ́ àwọn ọwọ̀n òrìṣà wọn túútúú,+ kí ẹ dáná sun àwọn òpó òrìṣà* wọn, kí ẹ sì gé ère àwọn ọlọ́run wọn+ tí wọ́n gbẹ́ lulẹ̀, kí orúkọ wọn lè pa rẹ́ kúrò níbẹ̀.+
4 “Ẹ ò gbọ́dọ̀ sin Jèhófà Ọlọ́run yín lọ́nà yẹn.+ 5 Kàkà bẹ́ẹ̀, ibikíbi tí Jèhófà Ọlọ́run yín bá yàn pé kí orúkọ rẹ̀ wà àti ibi tó bá ń gbé láàárín gbogbo ẹ̀yà yín ni kí ẹ ti máa wá a, ibẹ̀ sì ni kí ẹ máa lọ.+ 6 Ibẹ̀ ni kí ẹ máa mú àwọn ẹbọ sísun yín wá+ àti àwọn ẹbọ yín, àwọn ìdá mẹ́wàá yín,+ ọrẹ látọwọ́ yín,+ àwọn ọrẹ tí ẹ jẹ́jẹ̀ẹ́, àwọn ọrẹ àtinúwá+ yín àti àwọn àkọ́bí ọ̀wọ́ ẹran àti agbo ẹran yín.+ 7 Ibẹ̀ ni kí ẹ̀yin àti àwọn agbo ilé yín ti jẹun níwájú Jèhófà Ọlọ́run yín,+ kí ẹ sì máa yọ̀ nínú gbogbo ohun tí ẹ bá dáwọ́ lé,+ torí Jèhófà Ọlọ́run yín ti bù kún yín.
8 “Ẹ ò gbọ́dọ̀ ṣe bí a ṣe ń ṣe níbí lónìí, tí kálukú ń ṣe ohun tó dáa lójú ara rẹ̀,* 9 torí pé ẹ ò tíì dé ibi ìsinmi,+ ẹ ò sì tíì gba ogún tí Jèhófà Ọlọ́run yín fẹ́ fún yín. 10 Tí ẹ bá ti sọdá Jọ́dánì,+ tí ẹ sì wá ń gbé ní ilẹ̀ tí Jèhófà Ọlọ́run yín fẹ́ fún yín pé kó di tiyín, ó dájú pé ó máa mú kí ẹ sinmi lọ́wọ́ gbogbo àwọn ọ̀tá yín tó yí yín ká, ẹ ó sì máa gbé láìséwu.+ 11 Gbogbo ohun tí mò ń pa láṣẹ fún yín ni kí ẹ mú wá sí ibi tí Jèhófà Ọlọ́run yín yàn pé kí orúkọ rẹ̀ máa wà,+ ìyẹn àwọn ẹbọ sísun yín, àwọn ẹbọ yín, àwọn ìdá mẹ́wàá yín,+ ọrẹ látọwọ́ yín àti gbogbo ọrẹ tí ẹ jẹ́jẹ̀ẹ́ fún Jèhófà. 12 Kí ẹ máa yọ̀ níwájú Jèhófà Ọlọ́run yín,+ ẹ̀yin àti àwọn ọmọkùnrin yín, àwọn ọmọbìnrin yín, àwọn ẹrúkùnrin yín, àwọn ẹrúbìnrin yín àti ọmọ Léfì tó wà nínú àwọn ìlú* yín, torí wọn ò fún un ní ìpín tàbí ogún kankan pẹ̀lú yín.+ 13 Kí ẹ rí i pé ẹ ò rú àwọn ẹbọ sísun yín níbòmíì tí ẹ bá rí.+ 14 Ibi tí Jèhófà yàn nínú ọ̀kan lára àwọn ilẹ̀ tó jẹ́ ti ẹ̀yà yín nìkan ni kí ẹ ti rú àwọn ẹbọ sísun yín, ibẹ̀ sì ni kí ẹ ti ṣe gbogbo ohun tí mò ń pa láṣẹ fún yín.+
15 “Àmọ́ ìgbàkígbà tó bá wù yín* lẹ lè pa ẹran kí ẹ sì jẹ ẹ́,+ bí Jèhófà Ọlọ́run yín bá ṣe bù kún yín tó ní gbogbo ìlú* yín. Ẹni tó jẹ́ aláìmọ́ àti ẹni tó mọ́ lè jẹ ẹ́, bí ẹ ṣe máa ń jẹ egbin tàbí àgbọ̀nrín. 16 Àmọ́, ẹ ò gbọ́dọ̀ jẹ ẹ̀jẹ̀ rẹ̀;+ ṣe ni kí ẹ dà á sórí ilẹ̀ bí omi.+ 17 Ẹ ò gbọ́dọ̀ jẹ àwọn nǹkan yìí nínú àwọn ìlú* yín: ìdá mẹ́wàá ọkà yín, wáìnì tuntun yín, òróró yín, àwọn àkọ́bí lára ọ̀wọ́ ẹran àti agbo ẹran yín,+ èyíkéyìí lára àwọn ọrẹ tí ẹ jẹ́jẹ̀ẹ́, àwọn ọrẹ àtinúwá yín àti ọrẹ látọwọ́ yín. 18 Iwájú Jèhófà Ọlọ́run yín ni kí ẹ ti jẹ ẹ́, níbi tí Jèhófà Ọlọ́run yín bá yàn,+ ẹ̀yin àti ọmọkùnrin yín, ọmọbìnrin yín, ẹrúkùnrin yín àti ẹrúbìnrin yín àti ọmọ Léfì tó wà nínú àwọn ìlú* yín; kí ẹ sì máa yọ̀ níwájú Jèhófà Ọlọ́run yín nínú gbogbo ohun tí ẹ bá dáwọ́ lé. 19 Kí ẹ rí i pé ẹ ò gbàgbé ọmọ Léfì+ ní gbogbo ọjọ́ tí ẹ bá fi ń gbé lórí ilẹ̀ yín.
20 “Tí Jèhófà Ọlọ́run rẹ bá mú kí ilẹ̀ rẹ fẹ̀ sí i,+ bó ṣe ṣèlérí fún ọ gẹ́lẹ́,+ tí o wá ń sọ pé, ‘Mo fẹ́ jẹ ẹran,’ torí pé ẹran ń wù ọ́ jẹ,* o lè jẹ ẹ́ nígbàkigbà tó bá wù ọ́.*+ 21 Tí ibi tí Jèhófà Ọlọ́run rẹ yàn láti fi orúkọ rẹ̀ sí+ bá jìnnà sí ọ, kí o pa lára ọ̀wọ́ ẹran tàbí agbo ẹran rẹ tí Jèhófà fún ọ, bí mo ṣe pa á láṣẹ fún ọ, kí o sì jẹ ẹ́ nínú àwọn ìlú* rẹ nígbàkigbà tó bá wù ọ́.* 22 Kí o jẹ ẹ́ bí o ṣe máa ń jẹ egbin àti àgbọ̀nrín;+ ẹni tó jẹ́ aláìmọ́ àti ẹni tó mọ́ lè jẹ ẹ́. 23 Ṣáà ti pinnu pé o ò ní jẹ ẹ̀jẹ̀,+ má sì yẹ ìpinnu rẹ, torí pé ẹ̀jẹ̀ ni ẹ̀mí,*+ o ò sì gbọ́dọ̀ jẹ ẹ̀mí* pọ̀ mọ́ ẹran. 24 O ò gbọ́dọ̀ jẹ ẹ́. Ṣe ni kí o dà á sórí ilẹ̀ bí omi.+ 25 O ò gbọ́dọ̀ jẹ ẹ́, kí nǹkan lè máa lọ dáadáa fún ìwọ àti àwọn ọmọ rẹ lẹ́yìn rẹ, torí ò ń ṣe ohun tó tọ́ ní ojú Jèhófà. 26 Àwọn ohun mímọ́ tó jẹ́ tìrẹ àti àwọn ọrẹ tí o jẹ́jẹ̀ẹ́ nìkan ni kí o mú wá tí o bá wá sí ibi tí Jèhófà máa yàn. 27 Ibẹ̀ ni kí o ti rú àwọn ẹbọ sísun rẹ, ẹran àti ẹ̀jẹ̀ rẹ̀,+ lórí pẹpẹ Jèhófà Ọlọ́run rẹ, kí o sì da ẹ̀jẹ̀ àwọn ẹbọ rẹ sára pẹpẹ+ Jèhófà Ọlọ́run rẹ, ṣùgbọ́n o lè jẹ ẹran rẹ̀.
28 “Rí i pé ò ń tẹ̀ lé gbogbo ọ̀rọ̀ tí mò ń pa láṣẹ fún ọ yìí, kí nǹkan lè máa lọ dáadáa fún ìwọ àti àwọn ọmọ rẹ lẹ́yìn rẹ nígbà gbogbo, torí pé ò ń ṣe ohun tó dáa tó sì tọ́ ní ojú Jèhófà Ọlọ́run rẹ.
29 “Tí Jèhófà Ọlọ́run rẹ bá pa àwọn orílẹ̀-èdè tí o máa lé kúrò run,+ tí o sì wá ń gbé ilẹ̀ wọn, 30 rí i pé o ò kó sí ìdẹkùn lẹ́yìn tí wọ́n bá pa run kúrò níwájú rẹ. Má ṣe béèrè nípa àwọn ọlọ́run wọn pé, ‘Báwo ni àwọn orílẹ̀-èdè yìí ṣe máa ń sin àwọn ọlọ́run wọn? Ohun tí wọ́n ṣe lèmi náà máa ṣe.’+ 31 O ò gbọ́dọ̀ ṣe báyìí sí Jèhófà Ọlọ́run rẹ, torí gbogbo ohun tí Jèhófà kórìíra ni wọ́n máa ń ṣe sí àwọn ọlọ́run wọn, kódà wọ́n máa ń sun àwọn ọmọkùnrin wọn àti àwọn ọmọbìnrin wọn nínú iná sí àwọn ọlọ́run wọn.+ 32 Gbogbo ọ̀rọ̀ tí mò ń pa láṣẹ fún yín ni kí ẹ rí i pé ẹ tẹ̀ lé.+ Ẹ ò gbọ́dọ̀ fi kún un, ẹ ò sì gbọ́dọ̀ yọ kúrò nínú rẹ̀.+
13 “Tí ẹnì kan bá di wòlíì tàbí tó bẹ̀rẹ̀ sí í fi àlá sọ tẹ́lẹ̀ láàárín rẹ, tó sì fún ọ ní àmì tàbí tó sọ ohun kan tó fẹ́ ṣẹlẹ̀ fún ọ, 2 tí àmì náà tàbí ohun tó sọ fún ọ sì ṣẹ, tó wá ń sọ pé, ‘Jẹ́ ká tẹ̀ lé àwọn ọlọ́run míì,’ àwọn ọlọ́run tí o kò mọ̀, ‘sì jẹ́ ká máa sìn wọ́n,’ 3 o ò gbọ́dọ̀ fetí sí ọ̀rọ̀ wòlíì yẹn tàbí ti alálàá yẹn,+ torí Jèhófà Ọlọ́run yín ń dán yín wò+ kó lè mọ̀ bóyá ẹ fi gbogbo ọkàn yín àti gbogbo ara* yín nífẹ̀ẹ́ Jèhófà Ọlọ́run yín.+ 4 Jèhófà Ọlọ́run yín ni kí ẹ máa tọ̀ lẹ́yìn, òun ni kí ẹ máa bẹ̀rù, àwọn àṣẹ rẹ̀ ni kí ẹ máa pa mọ́, ohùn rẹ̀ sì ni kí ẹ máa fetí sí; òun ni kí ẹ máa sìn, òun sì ni kí ẹ rọ̀ mọ́.+ 5 Àmọ́ kí ẹ pa wòlíì yẹn tàbí alálàá yẹn,+ torí ó fẹ́ mú kí ẹ ṣọ̀tẹ̀ sí Jèhófà Ọlọ́run yín, kó lè mú yín kúrò ní ọ̀nà tí Jèhófà Ọlọ́run yín pa láṣẹ pé kí ẹ máa rìn, ẹni tó mú yín kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì, tó sì rà yín pa dà kúrò ní ilé ẹrú. Kí ẹ mú ohun tó burú kúrò láàárín yín.+
6 “Tí arákùnrin rẹ, ọmọ ìyá rẹ tàbí ọmọkùnrin rẹ tàbí ọmọbìnrin rẹ tàbí ìyàwó rẹ tí o fẹ́ràn tàbí ọ̀rẹ́ rẹ tímọ́tímọ́,* bá gbìyànjú láti tàn ọ́ ní ìkọ̀kọ̀ pé, ‘Jẹ́ ká lọ sin àwọn ọlọ́run míì,’+ àwọn ọlọ́run tí ìwọ àtàwọn baba ńlá rẹ kò mọ̀, 7 lára àwọn ọlọ́run àwọn èèyàn tó yí yín ká, ì báà jẹ́ nítòsí tàbí àwọn tó jìnnà sí yín, láti ìpẹ̀kun kan ilẹ̀ náà dé ìpẹ̀kun rẹ̀ kejì, 8 o ò gbọ́dọ̀ dá a lóhùn tàbí kí o fetí sí i,+ o ò gbọ́dọ̀ káàánú rẹ̀ tàbí kí o yọ́nú sí i, o ò sì gbọ́dọ̀ dáàbò bò ó; 9 kàkà bẹ́ẹ̀, ṣe ni kí o pa á.+ Ọwọ́ rẹ ni kó kọ́kọ́ bà á láti pa á, lẹ́yìn náà, kí gbogbo èèyàn dáwọ́ jọ kí wọ́n lè pa á.+ 10 O gbọ́dọ̀ sọ ọ́ lókùúta pa,+ torí ó fẹ́ mú ọ kúrò lọ́dọ̀ Jèhófà Ọlọ́run rẹ, ẹni tó mú ọ kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì, kúrò ní ilé ẹrú. 11 Nígbà náà, ẹ̀rù á ba gbogbo Ísírẹ́lì tí wọ́n bá gbọ́, wọn ò sì ní dán ohun tó burú bẹ́ẹ̀ wò mọ́ láàárín rẹ.+
12 “Nínú ọ̀kan lára àwọn ìlú rẹ, èyí tí Jèhófà Ọlọ́run rẹ fẹ́ fún ọ pé kí o máa gbé, tí o bá gbọ́ tí wọ́n sọ pé, 13 ‘Àwọn èèyàn tí kò ní láárí ti jáde láti àárín rẹ, kí wọ́n lè yí àwọn tó ń gbé ìlú wọn pa dà, wọ́n ń sọ pé: “Ẹ jẹ́ ká lọ sin àwọn ọlọ́run míì,” àwọn ọlọ́run tí ẹ kò mọ̀,’ 14 rí i pé o yẹ ọ̀rọ̀ náà wò, kí o ṣe ìwádìí fínnífínní, kí o sì béèrè nípa rẹ̀;+ tó bá jẹ́ pé òótọ́ ni wọ́n ṣe ohun ìríra yìí láàárín rẹ, 15 kí o rí i pé o fi idà pa àwọn tó ń gbé ìlú yẹn.+ Kí o fi idà pa ìlú náà àti gbogbo ohun tó wà nínú rẹ̀ run pátápátá, títí kan àwọn ẹran ọ̀sìn rẹ̀.+ 16 Kí o wá kó gbogbo ẹrù inú rẹ̀ jọ sí àárín ojúde ìlú náà, kí o sì fi iná sun ìlú náà, àwọn ẹrù yẹn á wá di odindi ọrẹ fún Jèhófà Ọlọ́run rẹ. Àwókù ni ìlú náà máa dà títí láé. O ò gbọ́dọ̀ tún un kọ́ láé. 17 O ò gbọ́dọ̀ mú ohunkóhun tí a máa pa run,*+ kí inú tó ń bí Jèhófà gidigidi lè rọ̀, kó lè ṣàánú rẹ, kó yọ́nú sí ọ, kó sì mú kí o pọ̀, bó ṣe búra fún àwọn baba ńlá rẹ gẹ́lẹ́.+ 18 Kí o máa pa gbogbo àṣẹ Jèhófà Ọlọ́run rẹ tí mò ń pa fún ọ lónìí mọ́, kí o lè máa ṣègbọràn sí i,* kí o lè máa ṣe ohun tó tọ́ ní ojú Jèhófà Ọlọ́run rẹ.+
14 “Ọmọ Jèhófà Ọlọ́run yín lẹ jẹ́. Ẹ ò gbọ́dọ̀ kọ ara yín ní abẹ+ tàbí kí ẹ fá iwájú orí yín* torí òkú.+ 2 Torí èèyàn mímọ́ lẹ jẹ́+ fún Jèhófà Ọlọ́run yín, Jèhófà sì ti yàn yín kí ẹ lè di èèyàn rẹ̀, ohun ìní rẹ̀ pàtàkì,* nínú gbogbo èèyàn tó wà láyé.+
3 “O ò gbọ́dọ̀ jẹ ohunkóhun tó ń ríni lára.+ 4 Àwọn ẹran tí ẹ lè jẹ nìyí:+ akọ màlúù, àgùntàn, ewúrẹ́, 5 àgbọ̀nrín, egbin, èsúwó, ẹ̀kìrì,* ẹtu, àgùntàn igbó àti àgùntàn orí àpáta. 6 Ẹ lè jẹ ẹran èyíkéyìí tí pátákò rẹ̀ là sí méjì, tó sì ń jẹ àpọ̀jẹ. 7 Àmọ́, ẹ ò gbọ́dọ̀ jẹ àwọn ẹran yìí tí wọ́n ń jẹ àpọ̀jẹ tàbí tí pátákò wọn là nìkan: ràkúnmí, ehoro àti gara orí àpáta, torí pé wọ́n ń jẹ àpọ̀jẹ ṣùgbọ́n pátákò wọn ò là. Aláìmọ́ ni wọ́n jẹ́ fún yín.+ 8 Bákan náà ni ẹlẹ́dẹ̀, torí pátákò rẹ̀ là, àmọ́ kì í jẹ àpọ̀jẹ. Aláìmọ́ ló jẹ́ fún yín. Ẹ ò gbọ́dọ̀ jẹ ẹran wọn, ẹ ò sì gbọ́dọ̀ fọwọ́ kan òkú wọn.
9 “Nínú gbogbo ohun tó ń gbé inú omi, èyí tí ẹ lè jẹ nìyí: Ẹ lè jẹ ohunkóhun tó bá ní lẹ́bẹ́ àti ìpẹ́.+ 10 Àmọ́ ẹ ò gbọ́dọ̀ jẹ ohunkóhun tí kò bá ní lẹ́bẹ́ àti ìpẹ́. Aláìmọ́ ló jẹ́ fún yín.
11 “Ẹ lè jẹ ẹyẹ èyíkéyìí tó bá mọ́. 12 Àmọ́ ẹ ò gbọ́dọ̀ jẹ àwọn ẹyẹ yìí: idì, idì ajẹja, igún dúdú,+ 13 àwòdì pupa, àwòdì dúdú, onírúurú ẹyẹ aṣọdẹ, 14 gbogbo onírúurú ẹyẹ ìwò, 15 ògòǹgò, òwìwí, ẹyẹ àkẹ̀, onírúurú àṣáǹwéwé, 16 òwìwí kékeré, òwìwí elétí gígùn, ògbùgbú, 17 ẹyẹ òfú, igún, ẹyẹ àgò, 18 ẹyẹ àkọ̀, onírúurú ẹyẹ wádòwádò, àgbìgbò àti àdán. 19 Gbogbo ẹ̀dá abìyẹ́ tó ń gbá yìn-ìn* pẹ̀lú jẹ́ aláìmọ́ fún yín. Ẹ ò gbọ́dọ̀ jẹ wọ́n. 20 Ẹ lè jẹ ẹ̀dá èyíkéyìí tó ń fò, tó sì mọ́.
21 “Ẹ ò gbọ́dọ̀ jẹ òkú ẹran èyíkéyìí.+ Ẹ lè fún àjèjì tó wà nínú àwọn ìlú* yín, kó sì jẹ ẹ́ tàbí kí ẹ tà á fún àjèjì. Torí pé èèyàn mímọ́ lẹ jẹ́ fún Jèhófà Ọlọ́run yín.
“Ẹ ò gbọ́dọ̀ se ọmọ ewúrẹ́ nínú wàrà ìyá rẹ̀.+
22 “O gbọ́dọ̀ rí i pé ò ń san ìdá mẹ́wàá gbogbo ohun tí irúgbìn rẹ bá ń mú jáde lọ́dọọdún.+ 23 Iwájú Jèhófà Ọlọ́run rẹ ni kí o ti máa jẹ ìdá mẹ́wàá ọkà rẹ, wáìnì tuntun rẹ, òróró rẹ àti àwọn àkọ́bí nínú ọ̀wọ́ ẹran àti agbo ẹran rẹ, ní ibi tó yàn pé kí orúkọ rẹ̀ máa wà,+ kí o lè kọ́ láti máa bẹ̀rù Jèhófà Ọlọ́run rẹ nígbà gbogbo.+
24 “Àmọ́ tí ọ̀nà ibẹ̀ bá jìn jù fún ọ, tó ò sì lè gbé e lọ sí ibi tí Jèhófà Ọlọ́run rẹ yàn pé kí orúkọ rẹ̀ máa wà+ torí pé ibẹ̀ jìnnà sí ọ, (torí pé Jèhófà Ọlọ́run rẹ máa bù kún ọ,) 25 o lè sọ ọ́ di owó, kí o wá mú owó náà dání, kí o sì rìnrìn àjò lọ sí ibi tí Jèhófà Ọlọ́run rẹ máa yàn. 26 O lè wá fi owó náà ra ohunkóhun tó bá wù ọ́,* bíi màlúù, àgùntàn, ewúrẹ́, wáìnì àtàwọn ohun mímu míì tó ní ọtí àti ohunkóhun tí o bá fẹ́;* kí o jẹ ẹ́ níbẹ̀ níwájú Jèhófà Ọlọ́run rẹ, kí o sì máa yọ̀, ìwọ àti agbo ilé rẹ.+ 27 O ò gbọ́dọ̀ gbàgbé ọmọ Léfì tó wà nínú àwọn ìlú rẹ,+ torí wọn ò fún un ní ìpín tàbí ogún kankan pẹ̀lú rẹ.+
28 “Ní òpin ọdún mẹ́ta-mẹ́ta, kí o kó gbogbo ìdá mẹ́wàá èso rẹ ní ọdún yẹn jáde, kí o sì kó o sínú àwọn ìlú rẹ.+ 29 Ọmọ Léfì tí wọn ò fún ní ìpín tàbí ogún kankan pẹ̀lú rẹ, àjèjì, ọmọ aláìníbaba* àti opó tí wọ́n wà nínú àwọn ìlú rẹ máa wá, wọ́n á sì jẹun yó,+ kí Jèhófà Ọlọ́run rẹ lè máa bù kún ọ nínú gbogbo ohun tí ò ń ṣe.+
15 “Ní òpin ọdún méje-méje, kí o máa ṣe ìtúsílẹ̀.+ 2 Bí ìtúsílẹ̀ náà ṣe máa rí nìyí: Kí gbogbo ẹni tí ọmọnìkejì rẹ̀ jẹ ní gbèsè má ṣe gbà á pa dà. Kó má sọ pé kí ọmọnìkejì rẹ̀ tàbí arákùnrin rẹ̀ san án pa dà, torí pé a máa kéde rẹ̀ pé ó jẹ́ ìtúsílẹ̀ fún Jèhófà.+ 3 O lè gbà á pa dà lọ́wọ́ àjèjì,+ àmọ́ kí o fagi lé gbèsè yòówù kí arákùnrin rẹ jẹ ọ́. 4 Ṣùgbọ́n, ẹnikẹ́ni nínú yín ò gbọ́dọ̀ tòṣì, torí ó dájú pé Jèhófà máa bù kún ọ+ ní ilẹ̀ tí Jèhófà Ọlọ́run rẹ fẹ́ fún ọ pé kí o jogún, 5 àfi tí o bá ṣègbọràn sí ohùn Jèhófà Ọlọ́run rẹ délẹ̀délẹ̀ nìkan, tí o sì rí i pé ò ń pa gbogbo àṣẹ yìí tí mò ń fún ọ lónìí mọ́.+ 6 Torí Jèhófà Ọlọ́run rẹ máa bù kún ọ bó ṣe ṣèlérí fún ọ, o sì máa yá ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè ní nǹkan,* àmọ́ kò ní sóhun tí á mú kí o yá nǹkan;+ o sì máa jọba lé ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè, àmọ́ wọn ò ní jọba lé ọ lórí.+
7 “Tí ọ̀kan lára àwọn arákùnrin rẹ bá di aláìní láàárín rẹ nínú ọ̀kan lára àwọn ìlú rẹ ní ilẹ̀ tí Jèhófà Ọlọ́run rẹ fẹ́ fún ọ, o ò gbọ́dọ̀ mú kí ọkàn rẹ le tàbí kí o háwọ́ sí arákùnrin rẹ tó jẹ́ aláìní.+ 8 Ṣe ni kí o lawọ́ sí i,+ kí o sì rí i dájú pé o yá a ní* ohunkóhun tó bá nílò tàbí tó ń jẹ ẹ́ níyà. 9 Rí i pé o ò gbin èrò ibi yìí sọ́kàn pé, ‘Ọdún keje, ọdún ìtúsílẹ̀, ti fẹ́rẹ̀ẹ́ dé,’+ kí o wá ṣahun sí arákùnrin rẹ tó jẹ́ aláìní, kí o má sì fún un ní nǹkan kan. Tó bá fi ẹjọ́ rẹ sun Jèhófà, ó ti di ẹ̀ṣẹ̀ sí ọ lọ́rùn nìyẹn.+ 10 Kí o lawọ́ sí i dáadáa,+ kí o* má sì ráhùn tí o bá ń fún un, torí èyí á mú kí Jèhófà Ọlọ́run rẹ bù kún ọ nínú gbogbo ohun tí o bá ń ṣe àtàwọn ohun tí o bá dáwọ́ lé.+ 11 Torí pé ìgbà gbogbo ni àwọn òtòṣì á máa wà ní ilẹ̀ rẹ.+ Ìdí nìyẹn tí mo fi ń pàṣẹ fún ọ pé, ‘Kí o lawọ́ dáadáa sí arákùnrin rẹ tí ìyà ń jẹ tó sì tòṣì ní ilẹ̀ rẹ.’+
12 “Tí wọ́n bá ta ọ̀kan lára àwọn èèyàn rẹ fún ọ, tó jẹ́ Hébérù, ì báà jẹ́ ọkùnrin tàbí obìnrin, tó sì ti fi ọdún mẹ́fà sìn ọ́, kí o dá a sílẹ̀ ní ọdún keje.+ 13 Tí o bá sì ti dá a sílẹ̀, má ṣe jẹ́ kó lọ lọ́wọ́ òfo. 14 Kí o lawọ́ sí i, kí o fún un látinú agbo ẹran rẹ, látinú ibi ìpakà rẹ àti látinú ibi tí o ti ń fún òróró àti wáìnì. Bí Jèhófà Ọlọ́run rẹ ṣe bù kún ọ gẹ́lẹ́ ni kí o ṣe fún un. 15 Rántí pé o di ẹrú ní ilẹ̀ Íjíbítì, Jèhófà Ọlọ́run rẹ sì rà ọ́ pa dà. Ìdí nìyẹn tí mo fi ń pa àṣẹ yìí fún ọ lónìí.
16 “Àmọ́ tó bá sọ fún ọ pé, ‘Mi ò ní kúrò lọ́dọ̀ rẹ!’ torí pé ó nífẹ̀ẹ́ ìwọ àti agbo ilé rẹ, tó sì jẹ́ pé inú rẹ̀ máa ń dùn nígbà tó wà lọ́dọ̀ rẹ,+ 17 kí o mú òòlu,* kí o sì fi dá etí rẹ̀ lu mọ́ ara ilẹ̀kùn, ó sì máa di ẹrú rẹ títí láé. Bẹ́ẹ̀ náà ni kí o ṣe fún ẹrúbìnrin rẹ. 18 Má kà á sí ìnira tí o bá dá a sílẹ̀, tó sì kúrò lọ́dọ̀ rẹ, torí pé ìlọ́po méjì iṣẹ́ tí alágbàṣe máa ṣe fún ọ ló ṣe ní ọdún mẹ́fà tó fi sìn ọ́, Jèhófà Ọlọ́run rẹ sì ti bù kún ọ nínú gbogbo ohun tí o ṣe.
19 “Gbogbo àkọ́bí tó jẹ́ akọ nínú ọ̀wọ́ ẹran rẹ àti nínú agbo ẹran rẹ ni kí o yà sọ́tọ̀ fún Jèhófà Ọlọ́run rẹ.+ O ò gbọ́dọ̀ fi àkọ́bí nínú ọ̀wọ́ ẹran* rẹ ṣe iṣẹ́ kankan, o ò sì gbọ́dọ̀ rẹ́ irun àkọ́bí nínú agbo ẹran rẹ. 20 Iwájú Jèhófà Ọlọ́run rẹ ni kí ìwọ àti agbo ilé rẹ ti máa jẹ ẹ́ lọ́dọọdún ní ibi tí Jèhófà máa yàn.+ 21 Àmọ́ tó bá ní àbùkù lára, bóyá ó jẹ́ arọ, afọ́jú tàbí tó ní oríṣi àbùkù míì tó le gan-an, o ò gbọ́dọ̀ fi rúbọ sí Jèhófà Ọlọ́run rẹ.+ 22 Inú àwọn ìlú* rẹ ni kí o ti jẹ ẹ́, aláìmọ́ àti ẹni tó mọ́ lè jẹ ẹ́, bí ẹni tó ń jẹ egbin tàbí àgbọ̀nrín.+ 23 Àmọ́ o ò gbọ́dọ̀ jẹ ẹ̀jẹ̀ rẹ̀;+ ṣe ni kí o dà á jáde sórí ilẹ̀ bí omi.+
16 “Máa rántí oṣù Ábíbù,* kí o sì máa ṣe ayẹyẹ Ìrékọjá fún Jèhófà Ọlọ́run rẹ,+ torí pé oṣù Ábíbù ni Jèhófà Ọlọ́run rẹ mú ọ kúrò ní Íjíbítì ní òru.+ 2 Kí o fi ẹran Ìrékọjá rúbọ sí Jèhófà Ọlọ́run rẹ,+ látinú agbo ẹran àti ọ̀wọ́ ẹran,+ ní ibi tí Jèhófà yàn pé kí orúkọ rẹ̀ máa wà.+ 3 O ò gbọ́dọ̀ jẹ ohunkóhun tó ní ìwúkàrà pẹ̀lú rẹ̀;+ ọjọ́ méje ni kí o fi jẹ búrẹ́dì aláìwú, ó jẹ́ oúnjẹ ìpọ́njú, torí pé ẹ kánjú kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì.+ Máa ṣe èyí ní gbogbo ìgbà tí o bá fi wà láàyè kí o lè máa rántí ọjọ́ tí o kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì.+ 4 Kò gbọ́dọ̀ sí àpòrọ́ kíkan lọ́wọ́ rẹ ní gbogbo ilẹ̀ rẹ fún ọjọ́ méje,+ bẹ́ẹ̀ ni ìkankan nínú ẹran tí o bá fi rúbọ ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ àkọ́kọ́ ò gbọ́dọ̀ ṣẹ́ kù di ọjọ́ kejì.+ 5 O ò gbọ́dọ̀ fi ẹran Ìrékọjá náà rúbọ nínú èyí tó bá kàn wù ọ́ nínú àwọn ìlú tí Jèhófà Ọlọ́run rẹ máa fún ọ. 6 Ṣùgbọ́n ibi tí Jèhófà Ọlọ́run rẹ bá yàn pé kí orúkọ rẹ̀ máa wà ni kí o ti ṣe é. Kí o fi ẹran Ìrékọjá náà rúbọ ní ìrọ̀lẹ́, gbàrà tí oòrùn bá wọ̀,+ ní déédéé àkókò tí o jáde kúrò ní Íjíbítì. 7 Kí o sè é, kí o sì jẹ ẹ́+ ní ibi tí Jèhófà Ọlọ́run rẹ bá yàn,+ kí o wá pa dà sí àgọ́ rẹ tí ilẹ̀ bá mọ́. 8 Ọjọ́ mẹ́fà ni kí o fi jẹ búrẹ́dì aláìwú, àpéjọ ọlọ́wọ̀ sì máa wà fún Jèhófà Ọlọ́run rẹ ní ọjọ́ keje. O ò gbọ́dọ̀ ṣiṣẹ́ kankan.+
9 “Kí o ka ọ̀sẹ̀ méje. Ìgbà tí o bá kọ́kọ́ ki dòjé bọ ọkà tó wà ní ìdúró ni kí o ti bẹ̀rẹ̀ sí í ka ọ̀sẹ̀ méje náà.+ 10 Kí o wá fi ọrẹ àtinúwá tí o mú wá ṣe Àjọyọ̀ Àwọn Ọ̀sẹ̀ fún Jèhófà Ọlọ́run rẹ,+ kí o mú un wá bí Jèhófà Ọlọ́run rẹ bá ṣe bù kún ọ tó.+ 11 Kí o sì máa yọ̀ níwájú Jèhófà Ọlọ́run rẹ, ìwọ àti ọmọkùnrin rẹ, ọmọbìnrin rẹ, ẹrúkùnrin rẹ, ẹrúbìnrin rẹ, ọmọ Léfì tó wà nínú àwọn ìlú* rẹ, àjèjì, ọmọ aláìníbaba* àti opó, tí wọ́n wà láàárín rẹ, ní ibi tí Jèhófà Ọlọ́run rẹ bá yàn pé kí orúkọ rẹ̀ máa wà.+ 12 Rántí pé o di ẹrú ní Íjíbítì,+ kí o máa pa àwọn ìlànà yìí mọ́, kí o sì máa tẹ̀ lé e.
13 “Ọjọ́ méje ni kí o fi ṣe Àjọyọ̀ Àtíbàbà,+ nígbà tí o bá kó ọkà rẹ jọ láti ibi ìpakà, tí o sì mú òróró àti wáìnì jáde láti ibi ìfúntí rẹ. 14 Máa yọ̀ nígbà àjọyọ̀ rẹ,+ ìwọ àti ọmọkùnrin rẹ, ọmọbìnrin rẹ, ẹrúkùnrin rẹ, ẹrúbìnrin rẹ, ọmọ Léfì, àjèjì, ọmọ aláìníbaba àti opó, tí wọ́n wà nínú àwọn ìlú rẹ. 15 Ọjọ́ méje ni kí o fi ṣe àjọyọ̀+ fún Jèhófà Ọlọ́run rẹ ní ibi tí Jèhófà bá yàn, torí Jèhófà Ọlọ́run rẹ máa bù kún gbogbo ohun tí o bá kórè àti gbogbo iṣẹ́ ọwọ́ rẹ,+ wàá sì máa láyọ̀ nígbà gbogbo.+
16 “Kí gbogbo ọkùnrin rẹ máa fara hàn níwájú Jèhófà Ọlọ́run lẹ́ẹ̀mẹta lọ́dún ní ibi tó bá yàn: ní Àjọyọ̀ Búrẹ́dì Aláìwú,+ Àjọyọ̀ Àwọn Ọ̀sẹ̀+ àti Àjọyọ̀ Àtíbàbà,+ kí ẹnì kankan nínú wọn má sì wá síwájú Jèhófà lọ́wọ́ òfo. 17 Kí kálukú yín mú ẹ̀bùn wá bí Jèhófà Ọlọ́run yín bá ṣe bù kún yín tó.+
18 “Kí o yan àwọn onídàájọ́+ àti àwọn olórí fún ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan ní gbogbo ìlú* tí Jèhófà Ọlọ́run rẹ máa fún ọ, kí wọ́n sì máa fi òdodo ṣèdájọ́ àwọn èèyàn náà. 19 O ò gbọ́dọ̀ ṣe èrú tí o bá ń dájọ́,+ o ò gbọ́dọ̀ ṣe ojúsàájú,+ o ò sì gbọ́dọ̀ gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀, torí àbẹ̀tẹ́lẹ̀ máa ń dí ọlọ́gbọ́n lójú,+ ó sì máa ń mú kí olódodo yí ọ̀rọ̀ po. 20 Máa ṣèdájọ́ òdodo, àní ìdájọ́ òdodo ni kí o máa ṣe,+ kí o lè máa wà láàyè, kí o sì lè gba ilẹ̀ tí Jèhófà Ọlọ́run rẹ máa fún ọ.
21 “O ò gbọ́dọ̀ gbin igi èyíkéyìí láti fi ṣe òpó òrìṣà*+ sẹ́gbẹ̀ẹ́ pẹpẹ Jèhófà Ọlọ́run rẹ tí o ṣe fún ara rẹ.
22 “O ò sì gbọ́dọ̀ ṣe ọwọ̀n òrìṣà fún ara rẹ,+ torí Jèhófà Ọlọ́run rẹ kórìíra rẹ̀.
17 “O ò gbọ́dọ̀ fi akọ màlúù tàbí àgùntàn tó ní àbùkù lára tàbí tí ohunkóhun ṣe, rúbọ sí Jèhófà Ọlọ́run rẹ, torí pé ohun ìríra ló máa jẹ́ lójú Jèhófà Ọlọ́run rẹ.+
2 “Ká sọ pé ọkùnrin tàbí obìnrin kan wà láàárín rẹ, nínú èyíkéyìí lára àwọn ìlú rẹ tí Jèhófà Ọlọ́run rẹ fẹ́ fún ọ, tó ń ṣe ohun tó burú lójú Jèhófà Ọlọ́run rẹ, tó sì ń tẹ májẹ̀mú rẹ̀ lójú,+ 3 tó wá yà bàrá, tó sì lọ ń jọ́sìn àwọn ọlọ́run míì, tó ń forí balẹ̀ fún wọn tàbí tó ń forí balẹ̀ fún oòrùn tàbí òṣùpá tàbí gbogbo ọmọ ogun ọ̀run,+ ohun tí mi ò pa láṣẹ.+ 4 Tí wọ́n bá sọ fún ọ tàbí tí o gbọ́ nípa rẹ̀, kí o wádìí ọ̀rọ̀ náà dáadáa. Tó bá jẹ́ òótọ́ ni+ ohun ìríra yìí ṣẹlẹ̀ ní Ísírẹ́lì, 5 kí o mú ọkùnrin tàbí obìnrin tó ṣe ohun burúkú yìí jáde wá sí ẹnubodè ìlú, kí ẹ sì sọ ọkùnrin tàbí obìnrin náà ní òkúta pa.+ 6 Ẹni méjì tàbí mẹ́ta ni kó jẹ́rìí sí i,*+ kí ẹ tó pa ẹni tí ikú tọ́ sí. Ẹ ò gbọ́dọ̀ pa á tó bá jẹ́ pé ẹnì kan ṣoṣo ló jẹ́rìí sí i.+ 7 Ọwọ́ àwọn ẹlẹ́rìí náà ni kó kọ́kọ́ bà á tí wọ́n bá fẹ́ pa á, lẹ́yìn náà kí gbogbo èèyàn dáwọ́ jọ láti pa á. Kí o mú ohun tó burú kúrò láàárín rẹ.+
8 “Tí ohun kan bá ṣẹlẹ̀ ní ọ̀kan lára àwọn ìlú rẹ, tí ẹjọ́ náà sì ṣòroó dá, bóyá ọ̀rọ̀ nípa ìtàjẹ̀sílẹ̀+ tàbí ẹnì kan fẹ́ gba ẹ̀tọ́ rẹ̀ tàbí àwọn kan hùwà ipá tàbí àwọn ẹjọ́ míì tó jẹ mọ́ fífa ọ̀rọ̀, kí o gbéra, kí o sì lọ sí ibi tí Jèhófà Ọlọ́run rẹ yàn.+ 9 Lọ bá àwọn àlùfáà, tí wọ́n jẹ́ ọmọ Léfì àti adájọ́+ tó ń gbẹ́jọ́ nígbà yẹn, kí o ro ẹjọ́ náà fún wọn, wọ́n á sì bá ọ dá a.+ 10 Ìdájọ́ tí wọ́n bá ṣe ní ibi tí Jèhófà yàn ni kí o tẹ̀ lé. Kí o rí i pé o ṣe gbogbo ohun tí wọ́n bá sọ fún ọ. 11 Kí o tẹ̀ lé òfin tí wọ́n bá fi hàn ọ́, kí o sì tẹ̀ lé ẹjọ́ tí wọ́n bá dá fún ọ.+ O ò gbọ́dọ̀ yà kúrò lórí ẹjọ́ tí wọ́n bá dá fún ọ, ì báà jẹ́ sí ọ̀tún tàbí sí òsì.+ 12 Ṣe ni kí ẹ pa ẹni tó bá ṣorí kunkun,* tó kọ̀ láti fetí sí àlùfáà tó ń bá Jèhófà Ọlọ́run rẹ ṣiṣẹ́ tàbí sí adájọ́ náà.+ Kí o mú ohun tó burú kúrò ní Ísírẹ́lì.+ 13 Gbogbo èèyàn á wá gbọ́, ẹ̀rù á bà wọ́n, wọn ò sì ní ṣorí kunkun mọ́.+
14 “Tí o bá dé ilẹ̀ tí Jèhófà Ọlọ́run rẹ fẹ́ fún ọ, tí o gbà á, tí o ti ń gbé ibẹ̀, tí o wá sọ pé, ‘Jẹ́ kí n yan ọba lé ara mi lórí, bíi ti àwọn orílẹ̀-èdè tó yí mi ká,’+ 15 nígbà náà, kí o rí i dájú pé ẹni tí Jèhófà Ọlọ́run rẹ bá yàn ni kí o fi jọba.+ Àárín àwọn arákùnrin rẹ ni kí o ti yan ẹni tó máa jọba. O ò gbọ́dọ̀ yan àjèjì, ẹni tí kì í ṣe arákùnrin rẹ ṣe olórí rẹ. 16 Àmọ́, kò gbọ́dọ̀ kó ẹṣin rẹpẹtẹ jọ fún ara rẹ̀,+ bẹ́ẹ̀ ni kò gbọ́dọ̀ ní kí àwọn èèyàn náà pa dà lọ sí Íjíbítì láti lọ kó ẹṣin sí i wá,+ torí Jèhófà ti sọ fún yín pé, ‘Ẹ ò gbọ́dọ̀ tún forí lé ọ̀nà yìí mọ́.’ 17 Kò sì gbọ́dọ̀ kó ìyàwó rẹpẹtẹ jọ fún ara rẹ̀, kí ọkàn rẹ̀ má bàa yí pa dà;+ bẹ́ẹ̀ ni kò gbọ́dọ̀ kó fàdákà àti wúrà rẹpẹtẹ jọ fún ara rẹ̀.+ 18 Tó bá ti jókòó sórí ìtẹ́ ìjọba rẹ̀, kó fi ọwọ́ ara rẹ̀ kọ ẹ̀dà Òfin yìí sínú ìwé* kan, látinú èyí tí àwọn ọmọ Léfì tí wọ́n jẹ́ àlùfáà tọ́jú.+
19 “Ọwọ́ rẹ̀ ni kó máa wà, kó sì máa kà á ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀,+ kó lè kọ́ láti máa bẹ̀rù Jèhófà Ọlọ́run rẹ̀, kó sì máa tẹ̀ lé gbogbo ọ̀rọ̀ inú Òfin yìí àti àwọn ìlànà yìí, kí o máa pa wọ́n mọ́.+ 20 Èyí ò ní jẹ́ kó gbé ọkàn rẹ̀ ga lórí àwọn arákùnrin rẹ̀, kò sì ní jẹ́ kó yà kúrò nínú àṣẹ náà, ì báà jẹ́ sí ọ̀tún tàbí sí òsì, kó lè pẹ́ lórí oyè, òun àti àwọn ọmọ rẹ̀ láàárín Ísírẹ́lì.
18 “Wọn ò ní fún àwọn àlùfáà tí wọ́n jẹ́ ọmọ Léfì àti gbogbo ẹ̀yà Léfì pátá ní ìpín tàbí ogún kankan ní Ísírẹ́lì. Wọ́n á máa jẹ lára àwọn ọrẹ àfinásun sí Jèhófà, èyí tó jẹ́ tirẹ̀.+ 2 Torí náà, wọn ò gbọ́dọ̀ ní ogún kankan láàárín àwọn arákùnrin wọn. Jèhófà ni ogún wọn, bó ṣe sọ fún wọn.
3 “Ohun tó máa jẹ́ ẹ̀tọ́ àwọn àlùfáà látọwọ́ àwọn èèyàn nìyí: Kí ẹnikẹ́ni tó bá fi ẹran rúbọ, ì báà jẹ́ akọ màlúù tàbí àgùntàn, fún àlùfáà ní apá, páárì ẹ̀rẹ̀kẹ́ àti àpòlúkù. 4 Kí o fún un ní àkọ́so ọkà rẹ, wáìnì tuntun rẹ, òróró rẹ àti irun tí o bá kọ́kọ́ rẹ́ lára agbo ẹran rẹ.+ 5 Jèhófà Ọlọ́run yín ti yan òun àti àwọn ọmọ rẹ̀ nínú gbogbo ẹ̀yà yín pé kí wọ́n máa ṣiṣẹ́ ní orúkọ Jèhófà nígbà gbogbo.+
6 “Àmọ́ tí ọmọ Léfì kan bá kúrò ní ọ̀kan lára àwọn ìlú yín ní Ísírẹ́lì, níbi tó ń gbé,+ tó sì wù ú* pé kó lọ sí ibi tí Jèhófà yàn,*+ 7 ó lè máa ṣiṣẹ́ níbẹ̀ ní orúkọ Jèhófà Ọlọ́run rẹ̀ bíi ti gbogbo àwọn arákùnrin rẹ̀ tí wọ́n jẹ́ ọmọ Léfì, tí wọ́n wà níbẹ̀ níwájú Jèhófà.+ 8 Iye oúnjẹ tí wọ́n bá pín fún àwọn yòókù ni kí wọ́n fún òun náà,+ ní àfikún sí ohun tó bá rí látinú ogún àwọn baba ńlá rẹ̀ tó tà.
9 “Tí ẹ bá ti dé ilẹ̀ tí Jèhófà Ọlọ́run yín fẹ́ fún yín, ẹ ò gbọ́dọ̀ bá àwọn orílẹ̀-èdè yẹn ṣe àwọn ohun ìríra tí wọ́n ń ṣe.+ 10 Ẹnì kankan láàárín yín ò gbọ́dọ̀ sun ọmọkùnrin rẹ̀ tàbí ọmọbìnrin rẹ̀ nínú iná,+ kò gbọ́dọ̀ woṣẹ́,+ kò gbọ́dọ̀ pidán,+ kò gbọ́dọ̀ wá àmì ohun tó fẹ́ ṣẹlẹ̀,+ kò gbọ́dọ̀ di oṣó,+ 11 kò gbọ́dọ̀ fi èèdì di àwọn ẹlòmíì, kò gbọ́dọ̀ wádìí ọ̀rọ̀ lọ́wọ́ abẹ́mìílò+ tàbí woṣẹ́woṣẹ́,+ kò sì gbọ́dọ̀ wádìí ọ̀rọ̀ lọ́wọ́ òkú.+ 12 Torí Jèhófà kórìíra ẹnikẹ́ni tó bá ń ṣe nǹkan wọ̀nyí, torí àwọn ohun ìríra yìí sì ni Jèhófà Ọlọ́run yín ṣe máa lé wọn kúrò níwájú yín. 13 Kí ẹ rí i pé ẹ jẹ́ aláìlẹ́bi níwájú Jèhófà Ọlọ́run yín.+
14 “Àwọn orílẹ̀-èdè tí ẹ máa lé kúrò yìí máa ń fetí sí àwọn tó ń pidán+ àti àwọn tó ń woṣẹ́,+ àmọ́ Jèhófà Ọlọ́run yín kò gbà kí ẹ ṣe ohunkóhun tó jọ èyí. 15 Jèhófà Ọlọ́run yín máa gbé wòlíì kan bí èmi dìde fún yín láàárín àwọn arákùnrin yín. Ẹ gbọ́dọ̀ fetí sí i.+ 16 Èyí jẹ́ ìdáhùn sí ohun tí ẹ béèrè lọ́wọ́ Jèhófà Ọlọ́run yín ní Hórébù, lọ́jọ́ tí ẹ pé jọ,*+ tí ẹ sọ pé, ‘Má ṣe jẹ́ kí n gbọ́ ohùn Jèhófà Ọlọ́run mi mọ́, má sì jẹ́ kí n rí iná ńlá yìí mọ́, kí n má bàa kú.’+ 17 Jèhófà wá sọ fún mi pé, ‘Ohun tí wọ́n sọ dáa. 18 Mo máa gbé wòlíì kan bíi tìẹ+ dìde fún wọn láàárín àwọn arákùnrin wọn, màá fi ọ̀rọ̀ mi sí i lẹ́nu,+ gbogbo ohun tí mo bá sì pa láṣẹ fún un ló máa sọ fún wọn.+ 19 Tí ẹnì kan kò bá fetí sí àwọn ọ̀rọ̀ mi tó máa sọ lórúkọ mi, ó dájú pé màá mú kí ẹni náà jíhìn.+
20 “‘Tí wòlíì èyíkéyìí bá kọjá àyè* rẹ̀, tó sọ̀rọ̀ lórúkọ mi, ọ̀rọ̀ tí mi ò pa láṣẹ fún un pé kó sọ tàbí tó sọ̀rọ̀ lórúkọ àwọn ọlọ́run mìíràn, wòlíì yẹn gbọ́dọ̀ kú.+ 21 Àmọ́, ẹ lè sọ lọ́kàn yín pé: “Báwo la ṣe máa mọ̀ pé Jèhófà kọ́ ló sọ ọ̀rọ̀ náà fún un?” 22 Tí wòlíì náà bá sọ̀rọ̀ lórúkọ Jèhófà, tí ọ̀rọ̀ náà kò sì ṣẹ tàbí tí ohun tó sọ kò ṣẹlẹ̀, á jẹ́ pé Jèhófà kọ́ ló sọ ọ̀rọ̀ náà. Ìkọjá àyè ló mú kó sọ ọ́. Ẹ ò gbọ́dọ̀ bẹ̀rù rẹ̀.’
19 “Tí Jèhófà Ọlọ́run rẹ bá ti pa àwọn orílẹ̀-èdè yìí run, ìyẹn àwọn tí Jèhófà Ọlọ́run rẹ fẹ́ fún ọ ní ilẹ̀ wọn, tí o ti lé wọn kúrò, tí o sì ti ń gbé inú àwọn ìlú wọn àti ilé wọn,+ 2 kí o ya ìlú mẹ́ta sọ́tọ̀ láàárín ilẹ̀ tí Jèhófà Ọlọ́run rẹ fẹ́ fún ọ pé kó di tìrẹ.+ 3 Kí o pín àwọn ilẹ̀ tí Jèhófà Ọlọ́run rẹ fún ọ pé kó di tìrẹ sí ọ̀nà mẹ́ta, kí o sì ṣe àwọn ọ̀nà, kí ẹnikẹ́ni tó bá pààyàn lè sá lọ sí ọ̀kan nínú àwọn ìlú náà.
4 “Ohun tó máa ṣẹlẹ̀ sí apààyàn tó bá sá lọ síbẹ̀ kó má bàa kú nìyí: Tó bá ṣèèṣì pa ẹnì kejì rẹ̀, tí kò sì kórìíra rẹ̀ tẹ́lẹ̀;+ 5 bóyá òun àti ẹnì kejì rẹ̀ jọ lọ ṣa igi nínú igbó, tó wá gbé àáké sókè láti gé igi, àmọ́ tí irin àáké náà fò yọ, tó ba ẹnì kejì rẹ̀, tó sì kú, kí apààyàn náà sá lọ sí ọ̀kan lára àwọn ìlú yìí, kó má bàa kú.+ 6 Àìjẹ́ bẹ́ẹ̀, ẹni tó ń gbẹ̀san ẹ̀jẹ̀+ lè fi ìbínú* lé apààyàn náà bá, kó sì pa á, torí pé ọ̀nà ìlú náà ti jìn jù. Àmọ́ kò yẹ kó pa á, torí pé kò kórìíra ẹnì kejì rẹ̀ tẹ́lẹ̀.+ 7 Ìdí nìyẹn tí mo fi ń pa á láṣẹ fún ọ pé: ‘Ya ìlú mẹ́ta sọ́tọ̀.’
8 “Tí Jèhófà Ọlọ́run rẹ bá mú kí ilẹ̀ rẹ pọ̀ sí i bó ṣe búra fún àwọn baba ńlá rẹ,+ tó sì ti fún ọ ní gbogbo ilẹ̀ tó ṣèlérí pé òun máa fún àwọn baba ńlá rẹ,+ 9 tí o bá ṣáà ti pa gbogbo àṣẹ yìí tí mò ń fún ọ lónìí mọ́ délẹ̀délẹ̀, pé kí o nífẹ̀ẹ́ Jèhófà Ọlọ́run rẹ, kí o sì máa rìn ní àwọn ọ̀nà rẹ̀ nígbà gbogbo,+ kí o fi ìlú mẹ́ta míì kún àwọn mẹ́ta yìí.+ 10 Èyí ò ní jẹ́ kí o ta ẹ̀jẹ̀ ẹni tí kò jẹ̀bi sílẹ̀+ ní ilẹ̀ tí Jèhófà Ọlọ́run rẹ máa fún ọ pé kí o jogún, o ò sì ní jẹ̀bi ẹ̀jẹ̀ kankan.+
11 “Àmọ́ tí ọkùnrin kan bá kórìíra ẹnì kejì rẹ̀,+ tó lúgọ dè é, tó ṣe é léṣe,* tó sì kú, tí ọkùnrin náà sì sá lọ sí ọ̀kan nínú àwọn ìlú yìí, 12 kí àwọn àgbààgbà ìlú rẹ̀ ránṣẹ́ pè é láti ibẹ̀, kí wọ́n sì fà á lé ẹni tó ń gbẹ̀san ẹ̀jẹ̀ lọ́wọ́, ó gbọ́dọ̀ kú.+ 13 O* ò gbọ́dọ̀ káàánú rẹ̀, ṣe ni kí o mú ẹ̀bi ẹ̀jẹ̀ ẹni tí kò mọwọ́ mẹsẹ̀ kúrò ní Ísírẹ́lì,+ kí nǹkan lè máa lọ dáadáa fún ọ.
14 “Tí o bá gba ogún rẹ ní ilẹ̀ tí Jèhófà Ọlọ́run fẹ́ fún ọ pé kó di tìrẹ, o ò gbọ́dọ̀ sún ààlà ọmọnìkejì rẹ sẹ́yìn + kúrò níbi tí àwọn baba ńlá fi sí.
15 “Ẹlẹ́rìí kan ṣoṣo kò tó láti dá ẹnì kan lẹ́bi* àṣìṣe tàbí ẹ̀ṣẹ̀ èyíkéyìí tó dá.+ Nípa ẹ̀rí* ẹni méjì tàbí ẹ̀rí ẹni mẹ́ta, kí ẹ fìdí ọ̀rọ̀ náà múlẹ̀.+ 16 Tí ẹlẹ́rìí èké kan bá jẹ́rìí lòdì sí ẹnì kan, tó sì fẹ̀sùn kàn án pé ó ṣe ohun tí kò dáa,+ 17 kí àwọn méjèèjì tó ń bára wọn fa ọ̀rọ̀ wá dúró níwájú Jèhófà, níwájú àwọn àlùfáà àti àwọn adájọ́ tí wọ́n á máa dájọ́ nígbà yẹn.+ 18 Kí àwọn adájọ́ náà wádìí ọ̀rọ̀ náà dáadáa,+ tó bá jẹ́ ẹlẹ́rìí èké ni ẹni tó jẹ́rìí sí ọ̀rọ̀ náà, tó sì fẹ̀sùn èké kan arákùnrin rẹ̀, 19 ohun tó gbèrò láti ṣe sí arákùnrin rẹ̀ ni kí ẹ ṣe sí i,+ kí ẹ sì mú ohun tó burú kúrò láàárín yín.+ 20 Tí àwọn yòókù bá gbọ́, ẹ̀rù á bà wọ́n, wọn ò sì ní ṣe irú ohun tó burú bẹ́ẹ̀ mọ́ láé láàárín rẹ.+ 21 O* ò gbọ́dọ̀ káàánú rẹ̀:+ Kí o gba ẹ̀mí* dípò ẹ̀mí,* ojú dípò ojú, eyín dípò eyín, ọwọ́ dípò ọwọ́, ẹsẹ̀ dípò ẹsẹ̀.+
20 “Tí o bá lọ bá àwọn ọ̀tá rẹ jagun, tí o sì rí àwọn ẹṣin, àwọn kẹ̀kẹ́ ẹṣin àti àwọn ọmọ ogun wọn tí wọ́n pọ̀ rẹpẹtẹ jù ọ́ lọ, má bẹ̀rù wọn, torí Jèhófà Ọlọ́run rẹ tó mú ọ kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì wà pẹ̀lú rẹ.+ 2 Tí ẹ bá fẹ́ lọ sójú ogun, kí àlùfáà lọ bá àwọn èèyàn náà, kó sì bá wọn sọ̀rọ̀.+ 3 Kó sọ fún wọn pé, ‘Ẹ gbọ́, ẹ̀yin ọmọ Ísírẹ́lì, àwọn ọ̀tá yín lẹ fẹ́ lọ bá jagun. Ẹ má ṣojo. Ẹ má bẹ̀rù, ẹ má sì jáyà, ẹ má ṣe jẹ́ kí jìnnìjìnnì bá yín nítorí wọn, 4 torí Jèhófà Ọlọ́run yín ń bá yín lọ kó lè jà fún yín láti ṣẹ́gun àwọn ọ̀tá yín, kó sì gbà yín là.’+
5 “Bákan náà, kí àwọn olórí sọ fún àwọn èèyàn náà pé, ‘Ta ló ti kọ́ ilé tuntun àmọ́ tí kò tíì ṣí i? Kó pa dà sí ilé rẹ̀. Àìjẹ́ bẹ́ẹ̀, ó lè kú sójú ogun, ẹlòmíì á sì ṣí ilé náà. 6 Ta ló sì ti gbin àjàrà, àmọ́ tí kò tíì bẹ̀rẹ̀ sí í gbádùn rẹ̀? Kó gbéra, kó sì pa dà sí ilé rẹ̀. Àìjẹ́ bẹ́ẹ̀, ó lè kú sójú ogun, ẹlòmíì á sì máa gbádùn àjàrà rẹ̀. 7 Ta ló sì ti ń fẹ́ obìnrin kan sọ́nà, àmọ́ tí kò tíì gbé e níyàwó? Kó gbéra, kó sì pa dà sí ilé rẹ̀.+ Àìjẹ́ bẹ́ẹ̀, ó lè kú sójú ogun, ọkùnrin míì á sì fi obìnrin náà ṣaya.’ 8 Kí àwọn olórí náà bi àwọn èèyàn náà pé, ‘Ta ni ẹ̀rù ń bà, tí àyà rẹ̀ sì ń já?+ Kó pa dà sí ilé rẹ̀, kó má bàa mú kí ọkàn àwọn arákùnrin rẹ̀ domi bíi tirẹ̀.’*+ 9 Tí àwọn olórí bá ti bá àwọn èèyàn náà sọ̀rọ̀ tán, kí wọ́n yan àwọn tó máa ṣe olórí àwọn ọmọ ogun láti darí àwọn èèyàn náà.
10 “Tí o bá sún mọ́ ìlú kan láti bá a jà, kí o fi ọ̀rọ̀ àlàáfíà ránṣẹ́ sí i.+ 11 Tó bá fún ọ lésì àlàáfíà, tó sì ṣí ọ̀nà fún ọ, gbogbo èèyàn tí o bá rí níbẹ̀ máa di tìẹ, wàá máa kó wọn ṣiṣẹ́, wọ́n á sì máa sìn ọ́.+ 12 Àmọ́ tó bá kọ̀, tí kò fún ọ lésì àlàáfíà, tó wá fẹ́ bá ọ jagun, kí o gbógun tì í, 13 ó sì dájú pé Jèhófà Ọlọ́run rẹ máa fi í lé ọ lọ́wọ́, kí o sì fi idà pa gbogbo ọkùnrin tó bá wà níbẹ̀. 14 Àmọ́ kí o kó àwọn obìnrin tó bá wà níbẹ̀ fún ara rẹ, àtàwọn ọmọdé, ẹran ọ̀sìn, gbogbo nǹkan tó bá wà nínú ìlú náà àti gbogbo ẹrù ibẹ̀,+ wàá sì máa lo gbogbo ohun ìní àwọn ọ̀tá rẹ tí Jèhófà Ọlọ́run rẹ fi lé ọ lọ́wọ́.+
15 “Ohun tí wàá ṣe sí gbogbo ìlú tó jìnnà gan-an sí ọ nìyẹn, àwọn ìlú tí kò sí nínú àwọn orílẹ̀-èdè tó wà nítòsí yìí. 16 Àmọ́ o ò gbọ́dọ̀ dá ohun eléèémí kankan sí ní ìlú àwọn èèyàn tí Jèhófà Ọlọ́run rẹ fẹ́ fún ọ pé kí o jogún.+ 17 Ṣe ni kí o pa wọ́n run pátápátá, ìyẹn àwọn ọmọ Hétì, àwọn Ámórì, àwọn ọmọ Kénáánì, àwọn Pérísì, àwọn Hífì àti àwọn ará Jébúsì,+ bí Jèhófà Ọlọ́run rẹ ṣe pa á láṣẹ fún ọ gẹ́lẹ́; 18 kí wọ́n má bàa kọ́ yín láti máa ṣe gbogbo ohun ìríra tí wọ́n ṣe sí àwọn ọlọ́run wọn, kí wọ́n wá mú kí ẹ ṣẹ Jèhófà Ọlọ́run yín.+
19 “Tí o bá gbógun ti ìlú kan, kí o lè gbà á, tó sì ti tó ọ̀pọ̀ ọjọ́ tí o ti ń bá a jà, o ò gbọ́dọ̀ yọ àáké ti àwọn igi rẹ̀ láti pa wọ́n run. O lè jẹ lára èso wọn, àmọ́ má ṣe gé wọn lulẹ̀.+ Ṣé ó yẹ kí o gbógun ti igi inú igbó bí ẹni ń gbógun ti èèyàn ni? 20 Igi tí o bá mọ̀ pé èso rẹ̀ kò ṣeé jẹ nìkan lo lè pa run. O lè gé e lulẹ̀, kí o sì fi ṣe àwọn ohun tí wàá fi gbógun ti ìlú tó fẹ́ bá ọ jagun títí o fi máa ṣẹ́gun rẹ̀.
21 “Tí wọ́n bá pa ẹnì kan sínú oko ní ilẹ̀ tí Jèhófà Ọlọ́run rẹ fẹ́ fún ọ pé kó di tìrẹ, tí o ò sì mọ ẹni tó pa á, 2 kí àwọn àgbààgbà àti àwọn adájọ́+ rẹ jáde lọ wọn ibi tí òkú náà wà sí àwọn ìlú tó yí i ká. 3 Kí àwọn àgbààgbà ìlú tó sún mọ́ òkú náà jù mú ọmọ màlúù kan látinú agbo ẹran, èyí tí kò tíì ṣiṣẹ́ rí, tí kò sì fa àjàgà rí. 4 Kí àwọn àgbààgbà ìlú yẹn wá mú ọmọ màlúù náà lọ sí àfonífojì tí omi ti ń ṣàn, lórí ilẹ̀ tí wọn ò tíì ro, tí wọn ò sì tíì gbin nǹkan sí, kí wọ́n sì ṣẹ́ ọrùn ọmọ màlúù náà ní àfonífojì yẹn.+
5 “Kí àwọn àlùfáà, àwọn ọmọ Léfì sì wá, torí Jèhófà Ọlọ́run rẹ ti yàn wọ́n pé kí wọ́n máa ṣe ìránṣẹ́ fún òun,+ kí wọ́n sì máa súre ní orúkọ Jèhófà.+ Wọ́n á sọ bí wọ́n á ṣe máa yanjú gbogbo ọ̀rọ̀ tó bá jẹ mọ́ ìwà ipá.+ 6 Kí gbogbo àgbààgbà ìlú tó sún mọ́ òkú náà jù wá fọ ọwọ́ wọn+ sórí ọmọ màlúù náà, èyí tí wọ́n ṣẹ́ ọrùn rẹ̀ ní àfonífojì, 7 kí wọ́n sì kéde pé, ‘Ọwọ́ wa kọ́ ló ta ẹ̀jẹ̀ yìí sílẹ̀, ojú wa ò sì rí i nígbà tí wọ́n ta á sílẹ̀. 8 Jèhófà, má ṣe kà á sí àwọn èèyàn rẹ Ísírẹ́lì lọ́rùn, àwọn tí o rà pa dà,+ má sì jẹ́ kí àwọn èèyàn rẹ Ísírẹ́lì jẹ̀bi ẹ̀jẹ̀ ẹni tí kò mọwọ́ mẹsẹ̀.’+ A ò sì ní ka ẹ̀bi ẹ̀jẹ̀ náà sí wọn lọ́rùn. 9 Èyí lo fi máa mú ẹ̀bi ẹ̀jẹ̀ ẹni tí kò mọwọ́ mẹsẹ̀ kúrò ní àárín rẹ, torí pé o ṣe ohun tó tọ́ lójú Jèhófà.
10 “Tí o bá lọ bá àwọn ọ̀tá rẹ jagun, tí Jèhófà Ọlọ́run rẹ bá ọ ṣẹ́gun wọn, tí o sì kó wọn lẹ́rú,+ 11 tí o wá rí obìnrin tó rẹwà láàárín àwọn tí o kó lẹ́rú, tó wù ọ́, tí o sì fẹ́ fi ṣaya, 12 kí o mú un wá sínú ilé rẹ. Kó sì fá orí rẹ̀, kó tọ́jú àwọn èékánná rẹ̀, 13 kó sì bọ́ aṣọ tó wọ̀ nígbà tó ṣì jẹ́ ẹrú, kó wá máa gbé ilé rẹ. Kó fi odindi oṣù kan sunkún torí bàbá àti ìyá rẹ̀,+ lẹ́yìn náà, o lè bá a lò pọ̀; wàá di ọkọ rẹ̀, á sì di ìyàwó rẹ. 14 Àmọ́ tí o ò bá fẹ́ràn rẹ̀, jẹ́ kó máa lọ+ ibikíbi tó bá wù ú.* Àmọ́ o ò gbọ́dọ̀ tà á gbowó, o ò sì gbọ́dọ̀ fìyà jẹ ẹ́, torí o ti dójú tì í.
15 “Tí ọkùnrin kan bá ní ìyàwó méjì, tó nífẹ̀ẹ́ ọ̀kan ju ìkejì lọ,* tí àwọn méjèèjì ti bímọ ọkùnrin fún un, tó sì jẹ́ pé ìyàwó tí kò fẹ́ràn yẹn ló bí àkọ́bí ọkùnrin,+ 16 lọ́jọ́ tó bá pín ogún fún àwọn ọmọ rẹ̀, kò ní sáyè fún un láti fi ọmọ ìyàwó tó fẹ́ràn ṣe àkọ́bí dípò ọmọ ìyàwó tí kò fẹ́ràn, èyí tó jẹ́ àkọ́bí gangan. 17 Kó gbà pé ọmọ ìyàwó tí òun kò fẹ́ràn ni àkọ́bí, kó fún un ní ìpín méjì nínú gbogbo ohun tó ní, torí òun ni ìbẹ̀rẹ̀ agbára ìbímọ rẹ̀. Òun ló ní ẹ̀tọ́ láti jẹ́ àkọ́bí.+
18 “Tí ọkùnrin kan bá ní ọmọ kan tó jẹ́ alágídí àti ọlọ̀tẹ̀, tí kì í gbọ́ràn sí bàbá àti ìyá rẹ̀ lẹ́nu,+ tí wọ́n sì ti gbìyànjú títí láti tọ́ ọ sọ́nà, àmọ́ tó kọ̀ tí ò gbọ́ tiwọn,+ 19 kí bàbá àti ìyá rẹ̀ mú un lọ sọ́dọ̀ àwọn àgbààgbà ní ẹnubodè ìlú rẹ̀, 20 kí wọ́n sì sọ fún àwọn àgbààgbà ìlú rẹ̀ pé, ‘Alágídí àti ọlọ̀tẹ̀ ni ọmọ wa yìí, kì í gbọ́ tiwa. Alájẹkì+ àti ọ̀mùtípara+ sì ni.’ 21 Kí gbogbo ọkùnrin ìlú rẹ̀ sọ ọ́ ní òkúta pa. Kí o mú ohun tó burú kúrò láàárín rẹ, tí gbogbo Ísírẹ́lì bá sì gbọ́, ẹ̀rù á bà wọ́n.+
22 “Tí ẹnì kan bá dẹ́ṣẹ̀, tó sì jẹ́ pé ikú ni ìyà ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, tí ẹ ti pa á,+ tí ẹ sì ti gbé e kọ́ sórí òpó igi,+ 23 ẹ má fi òkú rẹ̀ sílẹ̀ lórí òpó igi náà di ọjọ́ kejì.+ Kàkà bẹ́ẹ̀, kí ẹ rí i pé ẹ sin ín lọ́jọ́ yẹn, torí ẹni ègún ni ẹni tí a gbé kọ́ jẹ́ lójú Ọlọ́run,+ ẹ ò sì gbọ́dọ̀ sọ ilẹ̀ yín di aláìmọ́, èyí tí Jèhófà Ọlọ́run yín fẹ́ fún yín pé kí ẹ jogún.+
22 “Tí o bá rí akọ màlúù tàbí àgùntàn arákùnrin rẹ tó ń sọ nù lọ, má mọ̀ọ́mọ̀ mójú kúrò.+ Rí i dájú pé o mú un pa dà wá fún arákùnrin rẹ. 2 Àmọ́ tí arákùnrin rẹ ò bá gbé nítòsí rẹ tàbí tí o ò mọ̀ ọ́n, kí o mú ẹran náà lọ sí ilé rẹ, kó sì wà lọ́dọ̀ rẹ títí arákùnrin rẹ á fi máa wá a. Kí o sì dá a pa dà fún un.+ 3 Ohun tí wàá ṣe nìyẹn tí o bá rí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀, aṣọ rẹ̀ àti ohunkóhun tó sọ nù lọ́wọ́ arákùnrin rẹ. O ò gbọ́dọ̀ mójú kúrò.
4 “Tí o bá rí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ tàbí akọ màlúù arákùnrin rẹ tó ṣubú lójú ọ̀nà, má mọ̀ọ́mọ̀ mójú kúrò. Rí i dájú pé o bá a gbé ẹran náà dìde.+
5 “Obìnrin kò gbọ́dọ̀ wọ aṣọ ọkùnrin, bẹ́ẹ̀ ni ọkùnrin kò gbọ́dọ̀ wọ aṣọ obìnrin. Torí Jèhófà Ọlọ́run rẹ kórìíra ẹnikẹ́ni tó bá ń ṣe bẹ́ẹ̀.
6 “Tí o bá ṣàdédé rí ìtẹ́ ẹyẹ kan lójú ọ̀nà, tí àwọn ọmọ rẹ̀ tàbí àwọn ẹyin rẹ̀ wà nínú ìtẹ́ náà, ì báà jẹ́ lórí igi tàbí lórí ilẹ̀, tí àwọn ọmọ náà wà lábẹ́ ìyá wọn tàbí tó sàba lórí àwọn ẹyin náà, o ò gbọ́dọ̀ mú ìyá náà pẹ̀lú àwọn ọmọ rẹ̀.+ 7 Rí i dájú pé o jẹ́ kí ìyá wọn lọ, àmọ́ o lè kó àwọn ọmọ rẹ̀ sọ́dọ̀. Ohun tí o máa ṣe nìyí kí nǹkan lè máa lọ dáadáa fún ọ, kí ẹ̀mí rẹ sì lè gùn.
8 “Tí o bá kọ́ ilé tuntun, kí o ṣe ìgbátí sí òrùlé rẹ,+ kí o má bàa mú kí ilé rẹ jẹ̀bi ẹ̀jẹ̀ torí pé ẹnì kan já bọ́ látorí rẹ̀.
9 “O ò gbọ́dọ̀ fún oríṣi irúgbìn méjì sínú ọgbà àjàrà rẹ.+ Àìjẹ́ bẹ́ẹ̀, gbogbo ohun tó bá hù látinú irúgbìn tí o fún, títí kan àwọn ohun tó tinú ọgbà àjàrà náà jáde máa di ti ibi mímọ́.
10 “O ò gbọ́dọ̀ fi akọ màlúù àti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ túlẹ̀ pa pọ̀.+
11 “O ò gbọ́dọ̀ wọ aṣọ tí wọ́n fi irun àgùntàn àti ọ̀gbọ̀ hun pa pọ̀.+
12 “Kí o ṣe kókó wajawaja sí igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin aṣọ tí o bá wọ̀.+
13 “Tí ọkùnrin kan bá gbéyàwó, tó sì bá ìyàwó rẹ̀ lò pọ̀ àmọ́ tó wá kórìíra rẹ̀,* 14 tó sì fi ẹ̀sùn kàn án pé ó ti ṣe ìṣekúṣe, tó wá sọ ọ́ lórúkọ burúkú, tó ń sọ pé: ‘Mo ti fẹ́ obìnrin yìí, àmọ́ nígbà tí mo bá a lò pọ̀, mi ò rí ẹ̀rí tó fi hàn pé kò tíì ní ìbálòpọ̀ rí,’ 15 kí bàbá àti ìyá ọmọbìnrin náà mú ẹ̀rí wá fún àwọn àgbààgbà ní ẹnubodè ìlú náà láti fi hàn pé ọmọbìnrin náà ò tíì ní ìbálòpọ̀ rí. 16 Kí bàbá ọmọbìnrin náà sọ fún àwọn àgbààgbà pé, ‘Mo fún ọkùnrin yìí ní ọmọ mi pé kó fi ṣe aya, àmọ́ ó kórìíra rẹ̀,* 17 ó sì ń fẹ̀sùn kàn án pé oníṣekúṣe ni, ó ń sọ pé: “Mi ò rí ẹ̀rí pé ọmọbìnrin rẹ ò tíì ní ìbálòpọ̀ rí.” Ẹ̀rí ọ̀hún rèé o, pé ọmọbìnrin mi ò ní ìbálòpọ̀ rí.’ Kí wọ́n wá tẹ́ aṣọ náà síwájú àwọn àgbààgbà ìlú. 18 Kí àwọn àgbààgbà ìlú+ mú ọkùnrin náà, kí wọ́n sì bá a wí.+ 19 Kí wọ́n bu owó ìtanràn lé e, kó jẹ́ ọgọ́rùn-ún (100) ṣékélì* fàdákà, kí wọ́n sì kó o fún bàbá ọmọ náà, torí pé ọkùnrin náà ba wúńdíá Ísírẹ́lì lórúkọ jẹ́,+ ìyàwó rẹ̀ ló ṣì máa jẹ́. Ọkùnrin náà ò gbọ́dọ̀ kọ̀ ọ́ sílẹ̀ ní gbogbo ọjọ́ tó bá fi wà láàyè.
20 “Àmọ́ tó bá jẹ́ òótọ́ ni ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn án, tí kò sì sí ẹ̀rí pé ọmọbìnrin náà ò tíì ní ìbálòpọ̀ rí, 21 kí wọ́n mú ọmọbìnrin náà wá sí ẹnu ọ̀nà ilé bàbá rẹ̀, kí àwọn ọkùnrin ìlú rẹ̀ sì sọ ọ́ ní òkúta pa, torí ó ti hùwà tó ń dójú tini+ ní Ísírẹ́lì bó ṣe ṣe ìṣekúṣe* ní ilé bàbá rẹ̀.+ Kí ẹ mú ohun tó burú kúrò láàárín yín.+
22 “Tí ẹ bá rí ọkùnrin kan tó bá obìnrin tó jẹ́ ìyàwó ẹlòmíì sùn, ṣe ni kí ẹ pa àwọn méjèèjì, ọkùnrin tó bá obìnrin náà sùn pẹ̀lú obìnrin yẹn.+ Kí ẹ mú ohun tó burú kúrò ní Ísírẹ́lì.
23 “Tí wúńdíá kan bá ti ní àfẹ́sọ́nà, tí ọkùnrin míì wá rí wúńdíá náà nínú ìlú, tó sì bá a sùn, 24 kí ẹ mú àwọn méjèèjì wá sí ẹnubodè ìlú yẹn, kí ẹ sì sọ wọ́n ní òkúta pa, kí ẹ pa obìnrin náà torí pé kò kígbe nínú ìlú, kí ẹ sì pa ọkùnrin náà torí pé ó dójú ti ìyàwó ẹnì kejì rẹ̀.+ Kí ẹ mú ohun tó burú kúrò láàárín yín.
25 “Àmọ́ tó bá jẹ́ inú oko ni ọkùnrin náà ká obìnrin tó ní àfẹ́sọ́nà yẹn mọ́, tí ọkùnrin náà sì fi agbára mú un, tó sì bá a sùn, ọkùnrin tó bá a sùn yẹn nìkan ni kí ẹ pa, 26 àmọ́ ẹ ò gbọ́dọ̀ ṣe ohunkóhun fún obìnrin náà. Obìnrin náà kò dá ẹ̀ṣẹ̀ tó gba pé kí ẹ pa á. Ṣe ni ọ̀rọ̀ yìí dà bíi ti ọkùnrin kan tó lu ẹnì kejì rẹ̀, tó sì pa á.*+ 27 Torí pé inú oko ló ká obìnrin náà mọ́, obìnrin tó ti ní àfẹ́sọ́nà yẹn sì kígbe, àmọ́ kò sẹ́ni tó lè gbà á sílẹ̀.
28 “Tí ọkùnrin kan bá rí ọmọbìnrin kan tí kò tíì ní ìbálòpọ̀ rí, tí kò sì ní àfẹ́sọ́nà, tí ọkùnrin náà wá gbá a mú tó sì bá a sùn, tí ọ̀rọ̀ náà wá hàn síta,+ 29 kí ọkùnrin tó bá a sùn fún bàbá ọmọbìnrin náà ní àádọ́ta (50) ṣékélì fàdákà, obìnrin náà á sì di ìyàwó rẹ̀.+ Torí pé ọkùnrin náà ti dójú tì í, kò gbọ́dọ̀ kọ obìnrin náà sílẹ̀ ní gbogbo ọjọ́ tó bá fi wà láàyè.
30 “Ọkùnrin kankan ò gbọ́dọ̀ gba ìyàwó bàbá rẹ̀, kó má bàa dójú ti bàbá rẹ̀.*+
23 “Ọkùnrin èyíkéyìí tí wọ́n bá tẹ̀ lọ́dàá, tí wọ́n fọ́ kórópọ̀n rẹ̀ tàbí tí wọ́n gé ẹ̀yà ìbímọ rẹ̀ kúrò kò gbọ́dọ̀ wá sínú ìjọ Jèhófà.+
2 “Ọmọ àlè kankan ò gbọ́dọ̀ wá sínú ìjọ Jèhófà.+ Àní títí dé ìran rẹ̀ kẹwàá, àtọmọdọ́mọ rẹ̀ kankan ò gbọ́dọ̀ wá sínú ìjọ Jèhófà.
3 “Ọmọ Ámónì tàbí ọmọ Móábù kankan ò gbọ́dọ̀ wá sínú ìjọ Jèhófà.+ Àní títí dé ìran wọn kẹwàá, àtọmọdọ́mọ wọn kankan ò gbọ́dọ̀ wá sínú ìjọ Jèhófà láé, 4 torí pé wọn ò fún yín ní oúnjẹ àti omi láti fi ràn yín lọ́wọ́ nígbà tí ẹ kúrò ní Íjíbítì,+ wọ́n sì tún gba Báláámù ọmọ Béórì láti Pétórì ti Mesopotámíà pé kó wá gégùn-ún fún* yín.+ 5 Àmọ́ Jèhófà Ọlọ́run rẹ ò gbọ́ ti Báláámù.+ Kàkà bẹ́ẹ̀, Jèhófà Ọlọ́run rẹ yí ègún náà pa dà sí ìbùkún fún ọ,+ torí Jèhófà Ọlọ́run rẹ nífẹ̀ẹ́ rẹ.+ 6 O ò gbọ́dọ̀ wá ire wọn tàbí ìtẹ̀síwájú wọn ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ.+
7 “O ò gbọ́dọ̀ kórìíra ọmọ Édómù, torí arákùnrin rẹ ni.+
“O ò gbọ́dọ̀ kórìíra ọmọ Íjíbítì, torí o di àjèjì ní ilẹ̀ rẹ̀.+ 8 Ìran kẹta àwọn ọmọ tí wọ́n bá bí fún wọn lè wá sínú ìjọ Jèhófà.
9 “Tí o bá pàgọ́ láti gbógun ja àwọn ọ̀tá rẹ, kí o yẹra fún ohunkóhun tí kò dáa.*+ 10 Tí ọkùnrin kan bá di aláìmọ́ torí pé àtọ̀ dà lára rẹ̀ ní òru,+ kó kúrò nínú ibùdó, kó má sì pa dà síbẹ̀. 11 Tó bá di ìrọ̀lẹ́, kó fi omi wẹ̀, tí oòrùn bá sì ti wọ̀, kó pa dà sínú ibùdó.+ 12 Kí ibi ìkọ̀kọ̀* kan wà tí wàá máa lò lẹ́yìn ibùdó, ibẹ̀ sì ni kí o lọ. 13 Kí igi tó ṣeé fi gbẹ́lẹ̀ wà lára àwọn ohun èlò rẹ. Tí o bá lóṣòó ní ìta láti yàgbẹ́, kí o fi igi náà gbẹ́lẹ̀, kí o sì bo ìgbẹ́ rẹ. 14 Torí Jèhófà Ọlọ́run rẹ ń rìn kiri nínú ibùdó rẹ+ láti gbà ọ́, kó sì fi àwọn ọ̀tá rẹ lé ọ lọ́wọ́. Kí ibùdó rẹ máa wà ní mímọ́,+ kó má bàa rí ohunkóhun tí kò bójú mu láàárín rẹ, kó sì pa dà lẹ́yìn rẹ.
15 “O ò gbọ́dọ̀ fi ẹrú lé ọ̀gá rẹ̀ lọ́wọ́ tó bá sá kúrò lọ́dọ̀ ọ̀gá rẹ̀ wá sọ́dọ̀ rẹ. 16 Ó lè máa gbé láàárín rẹ níbikíbi tó bá yàn nínú ọ̀kan lára àwọn ìlú rẹ, níbikíbi tó bá wù ú. Má fìyà jẹ ẹ́.+
17 “Ìkankan nínú àwọn ọmọbìnrin Ísírẹ́lì ò gbọ́dọ̀ di aṣẹ́wó tẹ́ńpìlì,+ bẹ́ẹ̀ ni ìkankan nínú àwọn ọmọkùnrin Ísírẹ́lì ò gbọ́dọ̀ di aṣẹ́wó tẹ́ńpìlì.+ 18 O ò gbọ́dọ̀ mú owó tí wọ́n san fún obìnrin kan nídìí iṣẹ́ aṣẹ́wó tàbí owó tí wọ́n san fún ọkùnrin kan* nídìí iṣẹ́ aṣẹ́wó* wá sínú ilé Jèhófà Ọlọ́run rẹ láti fi san ẹ̀jẹ́, torí méjèèjì jẹ́ ohun ìríra lójú Jèhófà Ọlọ́run rẹ.
19 “O ò gbọ́dọ̀ gba èlé lọ́wọ́ arákùnrin rẹ,+ ì báà jẹ́ èlé lórí owó, lórí oúnjẹ tàbí ohunkóhun tí wọ́n ń gba èlé lé lórí. 20 O lè gba èlé lọ́wọ́ àjèjì,+ àmọ́ o ò gbọ́dọ̀ gba èlé lọ́wọ́ arákùnrin rẹ,+ kí Jèhófà Ọlọ́run rẹ lè máa bù kún ọ nínú gbogbo ohun tí o bá dáwọ́ lé ní ilẹ̀ tí o fẹ́ lọ gbà.+
21 “Tí o bá jẹ́jẹ̀ẹ́ fún Jèhófà Ọlọ́run rẹ,+ má ṣe lọ́ra láti san án.+ Torí ó dájú pé Jèhófà Ọlọ́run rẹ máa béèrè rẹ̀ lọ́wọ́ rẹ; àìjẹ́ bẹ́ẹ̀, ó máa di ẹ̀ṣẹ̀ sí ọ lọ́rùn.+ 22 Àmọ́ tí o ò bá jẹ́jẹ̀ẹ́, kò ní di ẹ̀ṣẹ̀ sí ọ lọ́rùn.+ 23 Máa mú ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ ṣẹ,+ tí o bá sì fi ẹnu ara rẹ jẹ́jẹ̀ẹ́ pé wàá ṣe ọrẹ àtinúwá fún Jèhófà Ọlọ́run rẹ, o gbọ́dọ̀ ṣe é.+
24 “Tí o bá lọ sínú ọgbà àjàrà ọmọnìkejì rẹ, o lè jẹ èso àjàrà débi tó bá tẹ́ ọ* lọ́rùn, àmọ́ o ò gbọ́dọ̀ kó ìkankan sínú àpò rẹ.+
25 “Tí o bá wọ inú oko ọkà ọmọnìkejì rẹ, o lè fọwọ́ ya àwọn ṣírí ọkà tó ti gbó, àmọ́ má yọ dòjé ti ọkà ọmọnìkejì rẹ.+
24 “Tí ọkùnrin kan bá fẹ́ obìnrin kan, àmọ́ tí obìnrin náà ò tẹ́ ẹ lọ́rùn torí ó rí ohun kan tí kò dáa nípa rẹ̀, kó kọ ìwé ẹ̀rí ìkọ̀sílẹ̀ fún un,+ kó fi lé e lọ́wọ́, kó sì ní kó kúrò ní ilé òun.+ 2 Tí obìnrin náà bá ti kúrò ní ilé rẹ̀, ó lè lọ fẹ́ ọkùnrin míì.+ 3 Tí ọkùnrin kejì bá kórìíra rẹ̀,* tó sì kọ ìwé ẹ̀rí ìkọ̀sílẹ̀ fún un, tó fi lé e lọ́wọ́, tó sì ní kó kúrò ní ilé òun tàbí tí ọkùnrin kejì tó fẹ́ ẹ bá kú, 4 ọkọ rẹ̀ àkọ́kọ́ tó lé e kúrò nílé ò ní lè gbà á pa dà mọ́ láti fi ṣe aya lẹ́yìn tó ti di aláìmọ́, torí ohun ìríra ló jẹ́ lójú Jèhófà. O ò gbọ́dọ̀ mú ẹ̀ṣẹ̀ wá sí ilẹ̀ tí Jèhófà Ọlọ́run rẹ fẹ́ fún ọ pé kí o jogún.
5 “Tí ọkùnrin kan bá ṣẹ̀ṣẹ̀ gbéyàwó, kò gbọ́dọ̀ dara pọ̀ mọ́ àwọn ọmọ ogun, wọn ò sì gbọ́dọ̀ yan àwọn iṣẹ́ míì fún un. Kó wà lómìnira fún ọdún kan, kó sì dúró sílé kó lè máa múnú ìyàwó rẹ̀ dùn.+
6 “Ẹnikẹ́ni ò gbọ́dọ̀ gba ọlọ tàbí ọmọ ọlọ láti fi ṣe ìdúró,*+ torí ohun tó ń gbé ẹ̀mí onítọ̀hún ró* ló fẹ́ gbà láti fi ṣe ìdúró yẹn.
7 “Tí ẹ bá rí ẹnì kan tó jí ọ̀kan* lára àwọn arákùnrin rẹ̀ tó jẹ́ ọmọ Ísírẹ́lì gbé, tó ti fìyà jẹ ẹ́, tó sì ti tà á,+ ṣe ni kí ẹ pa ẹni tó jí èèyàn gbé náà.+ Kí ẹ mú ohun tó burú kúrò láàárín yín.+
8 “Tí àrùn ẹ̀tẹ̀* bá yọ, kí ẹ rí i pé ẹ ṣe gbogbo ohun tí àwọn àlùfáà tó jẹ́ ọmọ Léfì bá ní kí ẹ ṣe.+ Kí ẹ rí i pé ẹ ṣe ohun tí mo pa láṣẹ fún wọn gẹ́lẹ́. 9 Ẹ rántí ohun tí Jèhófà Ọlọ́run yín ṣe sí Míríámù lójú ọ̀nà, nígbà tí ẹ kúrò ní Íjíbítì.+
10 “Tí o bá yá ọmọnìkejì rẹ ní ohunkóhun,+ o ò gbọ́dọ̀ wọ inú ilé lọ bá a láti gba ohun tó fẹ́ fi ṣe ìdúró. 11 Ìta ni kí o dúró sí, kí ẹni tí o yá ní nǹkan mú ohun tó fẹ́ fi ṣe ìdúró wá bá ọ níta. 12 Tí ẹni náà bá sì jẹ́ aláìní, ohun tó fi ṣe ìdúró ò gbọ́dọ̀ sun ọ̀dọ̀ rẹ mọ́jú.+ 13 Gbàrà tí oòrùn bá wọ̀ ni kí o rí i pé o dá ohun tó fi ṣe ìdúró pa dà fún un, kó lè rí aṣọ fi sùn,+ á sì súre fún ọ; èyí á sì jẹ́ òdodo lójú Jèhófà Ọlọ́run rẹ.
14 “O ò gbọ́dọ̀ rẹ́ alágbàṣe tó jẹ́ aláìní àti tálákà jẹ, ì báà jẹ́ ọ̀kan lára àwọn arákùnrin rẹ tàbí àjèjì tó wà ní ilẹ̀ rẹ, nínú àwọn ìlú* rẹ.+ 15 Ọjọ́ yẹn gan-an ni kí o fún un ní owó iṣẹ́ rẹ̀,+ kí oòrùn tó wọ̀, torí pé aláìní ni, owó iṣẹ́ yìí ló sì ń gbé ẹ̀mí* rẹ̀ ró. Àìjẹ́ bẹ́ẹ̀, ó máa fi ẹjọ́ rẹ sun Jèhófà, wàá sì jẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀.+
16 “Ẹ má pa àwọn bàbá torí ohun tí àwọn ọmọ wọn ṣe, ẹ má sì pa àwọn ọmọ torí ohun tí àwọn bàbá wọn ṣe.+ Kí a pa kálukú nítorí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀.+
17 “O ò gbọ́dọ̀ ṣe èrú tí o bá ń dá ẹjọ́ àjèjì tàbí ọmọ aláìníbaba,*+ o ò sì gbọ́dọ̀ gba aṣọ opó láti fi ṣe ìdúró.*+ 18 Rántí pé o di ẹrú ní Íjíbítì, Jèhófà Ọlọ́run rẹ sì rà ọ́ pa dà kúrò níbẹ̀.+ Ìdí nìyẹn tí mo fi ń pàṣẹ fún ọ pé kí o ṣe èyí.
19 “Tí o bá kórè oko rẹ, tí o sì gbàgbé ìtí ọkà kan sínú oko, o ò gbọ́dọ̀ pa dà lọ gbé e. Fi sílẹ̀ níbẹ̀ fún àjèjì, ọmọ aláìníbaba àti opó,+ kí Jèhófà Ọlọ́run rẹ lè máa bù kún ọ nínú gbogbo ohun tí o bá ń ṣe.+
20 “Tí o bá lu igi ólífì rẹ, o ò gbọ́dọ̀ ṣe bẹ́ẹ̀ sí àwọn ẹ̀ka rẹ̀. Kí o fi ohun tó bá ṣẹ́ kù sílẹ̀ fún àjèjì, ọmọ aláìníbaba àti opó.+
21 “Tí o bá kórè èso àjàrà inú ọgbà rẹ, o ò gbọ́dọ̀ pa dà lọ kó àwọn èso tó bá ṣẹ́ kù. Fi sílẹ̀ níbẹ̀ fún àjèjì, ọmọ aláìníbaba àti opó. 22 Rántí pé o di ẹrú ní ilẹ̀ Íjíbítì. Ìdí nìyẹn tí mo fi ń pàṣẹ fún ọ pé kí o ṣe èyí.
25 “Tí àwọn èèyàn bá ń bára wọn fa ọ̀rọ̀, kí wọ́n kó ara wọn lọ sọ́dọ̀ àwọn adájọ́,+ wọ́n á sì bá wọn dá ẹjọ́ wọn, wọ́n á dá olódodo láre, wọ́n á sì dá ẹni burúkú lẹ́bi.+ 2 Tí ẹgba bá tọ́ sí ẹni burúkú náà,+ kí adájọ́ dá a dọ̀bálẹ̀, kí wọ́n sì nà án níṣojú rẹ̀. Bí ohun tó ṣe bá ṣe burú tó ni kí iye ẹgba tó máa jẹ ṣe pọ̀ tó. 3 Ó lè nà án ní ogójì [40] ẹgba,+ àmọ́ kó má jù bẹ́ẹ̀ lọ. Tó bá nà án ní iye tó ju ìyẹn lọ, ó máa dójú ti arákùnrin rẹ níṣojú rẹ.
4 “O ò gbọ́dọ̀ di ẹnu akọ màlúù nígbà tó bá ń pa ọkà.+
5 “Tí àwọn arákùnrin bá jọ ń gbé, tí ọ̀kan nínú wọn sì kú láìní ọmọ, ìyàwó èyí tó kú kò gbọ́dọ̀ fẹ́ ẹni tí kì í ṣe mọ̀lẹ́bí ọkọ rẹ̀. Kí ẹ̀gbọ́n tàbí àbúrò ọkọ rẹ̀ lọ bá a, kó sì fi ṣe aya, kó ṣú u lópó.+ 6 Ọmọ tí obìnrin náà bá kọ́kọ́ bí á mú kí orúkọ arákùnrin rẹ̀ tó kú náà ṣì máa wà,+ kí orúkọ náà má bàa pa rẹ́ ní Ísírẹ́lì.+
7 “Àmọ́ tí ọkùnrin náà kò bá fẹ́ ṣú ìyàwó arákùnrin rẹ̀ lópó, kí ìyàwó arákùnrin rẹ̀ tó kú náà lọ bá àwọn àgbààgbà ní ẹnubodè ìlú, kó sì sọ fún wọn pé, ‘Arákùnrin ọkọ mi kò fẹ́ kí orúkọ arákùnrin rẹ̀ ṣì máa wà ní Ísírẹ́lì. Kò gbà láti ṣú mi lópó.’ 8 Kí àwọn àgbààgbà ìlú rẹ̀ wá pè é, kí wọ́n sì bá a sọ̀rọ̀. Tó bá ṣì takú, tó ń sọ pé, ‘Mi ò fẹ́ ẹ,’ 9 kí ìyàwó arákùnrin rẹ̀ tó kú náà wá sún mọ́ ọn níṣojú àwọn àgbààgbà, kó bọ́ bàtà ẹsẹ̀ ọkùnrin náà,+ kó tutọ́ sí i lójú, kó sì sọ pé, ‘Ohun tó yẹ kí wọ́n ṣe sí ọkùnrin tí kò fẹ́ kí ìdílé arákùnrin rẹ̀ ṣì máa wà nìyẹn.’ 10 Lẹ́yìn náà, wọ́n á mọ orúkọ ilé rẹ̀* sí ‘Ilé ẹni tí wọ́n bọ́ bàtà lẹ́sẹ̀ rẹ̀’ ní Ísírẹ́lì.
11 “Tí ọkùnrin méjì bá ń bára wọn jà, tí ìyàwó ọ̀kan sì wá gbèjà ọkọ rẹ̀ lọ́wọ́ ẹni tó ń lù ú, tó na ọwọ́ rẹ̀, tó sì rá ọkùnrin náà mú ní abẹ́, 12 ṣe ni kí o gé ọwọ́ obìnrin náà. O* ò gbọ́dọ̀ káàánú rẹ̀.
13 “O ò gbọ́dọ̀ ní oríṣi òkúta ìwọ̀n méjì nínú àpò rẹ,+ èyí tó tóbi àti èyí tó kéré. 14 O ò gbọ́dọ̀ ní oríṣi òṣùwọ̀n méjì nínú ilé rẹ,*+ èyí tó tóbi àti èyí tó kéré. 15 Ìwọ̀n tó péye tó sì tọ́ àti òṣùwọ̀n tó péye tó sì tọ́ ni kí o máa lò, kí o lè pẹ́ lórí ilẹ̀ tí Jèhófà Ọlọ́run rẹ fẹ́ fún ọ.+ 16 Torí Jèhófà Ọlọ́run rẹ kórìíra gbogbo ẹni tó ń ṣe nǹkan wọ̀nyí, tó ń rẹ́ ẹlòmíì jẹ.+
17 “Ẹ rántí ohun tí Ámálékì ṣe sí yín lójú ọ̀nà nígbà tí ẹ kúrò ní Íjíbítì,+ 18 bó ṣe pàdé yín lójú ọ̀nà nígbà tó ti rẹ̀ yín, tí ẹ ò sì lókun, tó sì gbógun ja gbogbo àwọn tó ń wọ́ rìn lẹ́yìn yín. Kò bẹ̀rù Ọlọ́run. 19 Tí Jèhófà Ọlọ́run rẹ bá ti mú kí o sinmi lọ́wọ́ gbogbo ọ̀tá rẹ tó yí ọ ká, ní ilẹ̀ tí Jèhófà Ọlọ́run rẹ fẹ́ fún ọ pé kí o jogún,+ kí o pa orúkọ Ámálékì rẹ́ kúrò lábẹ́ ọ̀run.+ O ò gbọ́dọ̀ gbàgbé.
26 “Tí o bá wá dé ilẹ̀ tí Jèhófà Ọlọ́run rẹ fẹ́ fún ọ pé kí o jogún, tí o ti gbà á, tí o sì ti ń gbé ibẹ̀, 2 kí o mú lára gbogbo ohun* tó bá kọ́kọ́ so ní ilẹ̀ náà, èyí tí o bá kó jọ ní ilẹ̀ rẹ tí Jèhófà Ọlọ́run rẹ fẹ́ fún ọ, kí o kó o sínú apẹ̀rẹ̀, kí o sì lọ sí ibi tí Jèhófà Ọlọ́run rẹ bá yàn pé kí orúkọ rẹ̀ máa wà.+ 3 Kí o lọ bá ẹni tó bá jẹ́ àlùfáà nígbà yẹn, kí o sì sọ fún un pé, ‘Mò ń sọ fún Jèhófà Ọlọ́run rẹ lónìí pé mo ti dé ilẹ̀ tí Jèhófà búra fún àwọn baba ńlá wa pé òun máa fún wa.’+
4 “Kí àlùfáà náà wá gba apẹ̀rẹ̀ náà lọ́wọ́ rẹ, kó sì gbé e síwájú pẹpẹ Jèhófà Ọlọ́run rẹ. 5 Kí o kéde níwájú Jèhófà Ọlọ́run rẹ pé, ‘Ará Arémíà tó ń lọ káàkiri* ni bàbá mi,+ ó lọ sí Íjíbítì,+ ó sì di àjèjì tó ń gbé níbẹ̀, òun àti àwọn díẹ̀ tí wọ́n jẹ́ ará ilé rẹ̀.+ Àmọ́ ibẹ̀ ló ti di orílẹ̀-èdè ńlá, tó lágbára, tó sì pọ̀ rẹpẹtẹ.+ 6 Àwọn ọmọ Íjíbítì fìyà jẹ wá, wọ́n pọ́n wa lójú, wọ́n sọ wá di ẹrú tí wọ́n ń lò nílòkulò.+ 7 A wá bẹ̀rẹ̀ sí í ké pe Jèhófà, Ọlọ́run àwọn baba ńlá wa, Jèhófà sì gbọ́ ohùn wa, ó rí bí wọ́n ṣe ń fìyà jẹ wá, bá a ṣe ń dààmú àti bí wọ́n ṣe ń pọ́n wa lójú.+ 8 Níkẹyìn, Jèhófà fi ọwọ́ agbára mú wa kúrò ní Íjíbítì, pẹ̀lú apá tó nà jáde,+ àwọn nǹkan tó ń bani lẹ́rù, àwọn àmì àtàwọn iṣẹ́ ìyanu.+ 9 Ó mú wa wá sí ibí yìí, ó sì fún wa ní ilẹ̀ yìí, ilẹ̀ tí wàrà àti oyin ti ń ṣàn.+ 10 Ní báyìí, mo ti mú àkọ́so èso ilẹ̀ tí Jèhófà fún mi wá.’+
“Kí o kó o síwájú Jèhófà Ọlọ́run rẹ, kí o sì tẹrí ba níwájú Jèhófà Ọlọ́run rẹ. 11 Kí o wá máa yọ̀ torí gbogbo nǹkan rere tí Jèhófà Ọlọ́run rẹ fún ìwọ àti agbo ilé rẹ, ìwọ àti ọmọ Léfì àti àjèjì tó bá wà láàárín rẹ.+
12 “Tí o bá ti kó gbogbo ìdá mẹ́wàá+ èso ilẹ̀ rẹ jọ tán ní ọdún kẹta, ọdún ìdá mẹ́wàá, kí o fún ọmọ Léfì, àjèjì, ọmọ aláìníbaba* àti opó, kí wọ́n sì jẹ ẹ́ yó nínú àwọn ìlú* rẹ.+ 13 Kí o wá sọ níwájú Jèhófà Ọlọ́run rẹ pé, ‘Mo ti kó ìpín mímọ́ kúrò nínú ilé mi, mo sì ti fún ọmọ Léfì, àjèjì, ọmọ aláìníbaba àti opó,+ bí o ṣe pa á láṣẹ fún mi gẹ́lẹ́. Mi ò tẹ àwọn àṣẹ rẹ lójú, mi ò sì pa wọ́n tì. 14 Mi ò jẹ nínú rẹ̀ nígbà tí mò ń ṣọ̀fọ̀, mi ò sì mú ìkankan kúrò nínú rẹ̀ nígbà tí mo jẹ́ aláìmọ́, bẹ́ẹ̀ ni mi ò lò lára rẹ̀ torí òkú. Mo fetí sí ohùn Jèhófà Ọlọ́run mi, mo sì ti ṣe gbogbo ohun tí o pa láṣẹ fún mi. 15 Wá bojú wolẹ̀ láti ọ̀run, ibi mímọ́ rẹ tí ò ń gbé, kí o sì bù kún àwọn èèyàn rẹ Ísírẹ́lì àti ilẹ̀ tí o fún wa,+ bí o ṣe búra fún àwọn baba ńlá wa,+ ilẹ̀ tí wàrà àti oyin ti ń ṣàn.’+
16 “Jèhófà Ọlọ́run rẹ ń pa á láṣẹ fún ọ lónìí pé kí o máa pa àwọn ìlànà àtàwọn ìdájọ́ yìí mọ́. Kí o máa tẹ̀ lé wọn, kí o sì máa fi gbogbo ọkàn rẹ+ àti gbogbo ara* rẹ pa á mọ́. 17 Lónìí, o ti gbọ́ tí Jèhófà kéde pé òun máa di Ọlọ́run rẹ, tí o bá ń rìn ní àwọn ọ̀nà rẹ̀, tí ò ń pa ìlànà rẹ̀ mọ́+ àti àwọn àṣẹ rẹ̀+ pẹ̀lú àwọn ìdájọ́ rẹ̀,+ tí o sì ń fetí sí ohùn rẹ̀. 18 Jèhófà sì ti gbọ́ ohun tí o kéde lónìí pé o máa di èèyàn rẹ̀, ohun ìní rẹ̀ pàtàkì,*+ bó ṣe ṣèlérí fún ọ gẹ́lẹ́ àti pé o máa pa gbogbo àṣẹ rẹ̀ mọ́, 19 pé òun máa gbé ọ ga ju gbogbo orílẹ̀-èdè yòókù tó dá,+ pé òun á mú kí àwọn èèyàn máa yìn ọ́, òun sì máa mú kí o ní òkìkí àti ògo, bó ṣe ṣèlérí fún ọ gẹ́lẹ́, tí o bá fi hàn pé o jẹ́ èèyàn mímọ́ lójú Jèhófà Ọlọ́run rẹ.”+
27 Mósè pẹ̀lú àwọn àgbààgbà Ísírẹ́lì wá pàṣẹ fún àwọn èèyàn náà pé: “Kí ẹ pa gbogbo àṣẹ tí mò ń pa fún yín lónìí mọ́. 2 Ní ọjọ́ tí ẹ bá sọdá Jọ́dánì sí ilẹ̀ tí Jèhófà Ọlọ́run yín fẹ́ fún yín, kí ẹ to àwọn òkúta ńláńlá jọ, kí ẹ sì rẹ́ ẹ.*+ 3 Kí ẹ wá kọ gbogbo ọ̀rọ̀ Òfin yìí sára wọn tí ẹ bá ti sọdá, kí ẹ lè wọ ilẹ̀ tí Jèhófà Ọlọ́run yín fẹ́ fún yín, ilẹ̀ tí wàrà àti oyin ti ń ṣàn, bí Jèhófà Ọlọ́run àwọn baba ńlá yín ṣe ṣèlérí fún yín gẹ́lẹ́.+ 4 Tí ẹ bá ti sọdá Jọ́dánì, kí ẹ to àwọn òkúta yìí sórí Òkè Ébálì,+ kí ẹ sì rẹ́ ẹ,* bí mo ṣe ń pa á láṣẹ fún yín lónìí. 5 Kí ẹ tún mọ pẹpẹ kan síbẹ̀ fún Jèhófà Ọlọ́run yín, òkúta ni kí ẹ fi mọ ọ́n. Ẹ má fi irin gbẹ́ ẹ.+ 6 Odindi òkúta ni kí ẹ fi mọ pẹpẹ Jèhófà Ọlọ́run yín, kí ẹ sì rú àwọn ẹbọ sísun sí Jèhófà Ọlọ́run yín lórí rẹ̀. 7 Kí ẹ rú àwọn ẹbọ ìrẹ́pọ̀,+ kí ẹ jẹ ẹ́ níbẹ̀,+ kí ẹ sì máa yọ̀ níwájú Jèhófà Ọlọ́run yín.+ 8 Kí ẹ kọ gbogbo ọ̀rọ̀ inú Òfin yìí sára àwọn òkúta náà, kó sì hàn kedere.”+
9 Mósè àtàwọn àlùfáà tí wọ́n jẹ́ ọmọ Léfì wá sọ fún gbogbo Ísírẹ́lì pé: “Ẹ dákẹ́ jẹ́ẹ́, kí ẹ sì fetí sílẹ̀, ẹ̀yin ọmọ Ísírẹ́lì. Ẹ ti di èèyàn Jèhófà Ọlọ́run yín lónìí.+ 10 Kí ẹ máa fetí sí ohùn Jèhófà Ọlọ́run yín, kí ẹ máa pa àwọn àṣẹ+ àti ìlànà rẹ̀ mọ́, èyí tí mò ń pa láṣẹ fún yín lónìí.”
11 Mósè pàṣẹ fún àwọn èèyàn náà lọ́jọ́ yẹn pé: 12 “Àwọn ẹ̀yà yìí ló máa dúró lórí Òkè Gérísímù+ láti súre fún àwọn èèyàn náà tí ẹ bá ti sọdá Jọ́dánì: Síméónì, Léfì, Júdà, Ísákà, Jósẹ́fù àti Bẹ́ńjámínì. 13 Àwọn ẹ̀yà yìí ló sì máa dúró lórí Òkè Ébálì+ láti kéde ègún: Rúbẹ́nì, Gádì, Áṣérì, Sébúlúnì, Dánì àti Náfútálì. 14 Kí àwọn ọmọ Léfì gbóhùn sókè dáadáa, kí wọ́n sì sọ fún gbogbo Ísírẹ́lì pé:+
15 “‘Ègún ni fún ẹni tó bá gbẹ́ ère+ tàbí tó ṣe ère onírin,*+ tó jẹ́ ohun ìríra lójú Jèhófà,+ iṣẹ́ ọwọ́ oníṣẹ́ ọnà,* tó sì gbé e pa mọ́.’ (Kí gbogbo èèyàn sì sọ pé, ‘Àmín!’*)
16 “‘Ègún ni fún ẹni tó bá fojú kéré bàbá àti ìyá rẹ̀.’+ (Kí gbogbo èèyàn sì sọ pé, ‘Àmín!’)
17 “‘Ègún ni fún ẹni tó bá sún ààlà ọmọnìkejì rẹ̀.’+ (Kí gbogbo èèyàn sì sọ pé, ‘Àmín!’)
18 “‘Ègún ni fún ẹni tó bá mú kí afọ́jú ṣìnà.’+ (Kí gbogbo èèyàn sì sọ pé, ‘Àmín!’)
19 “‘Ègún ni fún ẹni tó bá ṣe èrú nínú ẹjọ́+ àjèjì, ọmọ aláìníbaba* tàbí opó.’+ (Kí gbogbo èèyàn sì sọ pé, ‘Àmín!’)
20 “‘Ègún ni fún ẹni tó bá bá ìyàwó bàbá rẹ̀ sùn, torí ó ti dójú ti bàbá rẹ̀.’*+ (Kí gbogbo èèyàn sì sọ pé, ‘Àmín!’)
21 “‘Ègún ni fún ẹni tó bá bá ẹranko èyíkéyìí lò pọ̀.’+ (Kí gbogbo èèyàn sì sọ pé, ‘Àmín!’)
22 “‘Ègún ni fún ẹni tó bá bá arábìnrin rẹ̀ sùn, ì báà jẹ́ ọmọ bàbá rẹ̀ tàbí ọmọ ìyá rẹ̀.’+ (Kí gbogbo èèyàn sì sọ pé, ‘Àmín!’)
23 “‘Ègún ni fún ẹni tó bá bá ìyá ìyàwó rẹ̀ sùn.’+ (Kí gbogbo èèyàn sì sọ pé, ‘Àmín!’)
24 “‘Ègún ni fún ẹni tó bá lúgọ de ọmọnìkejì rẹ̀, tó sì pa á.’+ (Kí gbogbo èèyàn sì sọ pé, ‘Àmín!’)
25 “‘Ègún ni fún ẹni tó bá gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀ láti pa ẹni tí kò mọwọ́ mẹsẹ̀.’*+ (Kí gbogbo èèyàn sì sọ pé, ‘Àmín!’)
26 “‘Ègún ni fún ẹni tí kò bá pa àwọn ọ̀rọ̀ inú Òfin yìí mọ́ láti fi hàn pé ó fara mọ́ wọn.’+ (Kí gbogbo èèyàn sì sọ pé, ‘Àmín!’)
28 “Tí o bá ń pa gbogbo àṣẹ Jèhófà Ọlọ́run rẹ tí mò ń pa fún ọ lónìí mọ́ délẹ̀délẹ̀, kí o lè máa rí i pé ò ń fetí sí ohùn rẹ̀, ó dájú pé Jèhófà Ọlọ́run rẹ máa gbé ọ ga ju gbogbo orílẹ̀-èdè yòókù tó wà láyé+ lọ. 2 Gbogbo ìbùkún yìí máa jẹ́ tìrẹ, ó sì máa bá ọ,+ torí pé ò ń fetí sí ohùn Jèhófà Ọlọ́run rẹ:
3 “Ìbùkún ni fún ọ nínú ìlú, ìbùkún sì ni fún ọ nínú pápá.+
4 “Ìbùkún ni fún àwọn ọmọ*+ rẹ àti èso ilẹ̀ rẹ àtàwọn ọmọ ẹran ọ̀sìn rẹ, ọmọ màlúù àti àgùntàn+ rẹ.
5 “Ìbùkún ni fún apẹ̀rẹ̀+ rẹ àti abọ́ tí o fi ń po nǹkan.+
6 “Ìbùkún ni fún ọ tí o bá wọlé, ìbùkún sì ni fún ọ tí o bá jáde.
7 “Jèhófà máa mú kí o ṣẹ́gun+ àwọn ọ̀tá rẹ tí wọ́n dìde sí ọ. Ọ̀nà kan ni wọ́n á gbà yọ sí ọ láti bá ọ jà, àmọ́ ọ̀nà méje ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni wọ́n á gbà sá kúrò lọ́dọ̀ rẹ.+ 8 Jèhófà máa pàṣẹ ìbùkún sórí àwọn ilé ìkẹ́rùsí+ rẹ àti gbogbo ohun tí o bá dáwọ́ lé, ó sì dájú pé Jèhófà Ọlọ́run rẹ máa bù kún ọ ní ilẹ̀ tó fẹ́ fún ọ. 9 Jèhófà máa fi ọ́ ṣe èèyàn mímọ́ fún ara rẹ̀,+ bó ṣe búra fún ọ+ gẹ́lẹ́, torí pé ò ń pa àwọn àṣẹ Jèhófà Ọlọ́run rẹ mọ́, o sì ń rìn ní àwọn ọ̀nà rẹ̀. 10 Gbogbo èèyàn tó wà ní ayé á sì rí i pé orúkọ Jèhófà ni wọ́n fi ń pè ọ́,+ wọ́n á sì máa bẹ̀rù rẹ.+
11 “Jèhófà máa mú kí o ní ọmọ tó pọ̀ rẹpẹtẹ, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹran ọ̀sìn àti ilẹ̀ tó ń mú èso jáde+ ní ilẹ̀ tí Jèhófà búra pé òun máa fún àwọn baba ńlá rẹ.+ 12 Jèhófà máa ṣí ọ̀run, ilé ìkẹ́rùsí rẹ̀ tó dáa fún ọ, láti rọ òjò sórí ilẹ̀ rẹ ní àkókò+ rẹ̀, kó sì bù kún gbogbo iṣẹ́ ọwọ́ rẹ. O máa yá ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè ní nǹkan, àmọ́ kò ní sóhun tó máa mú kí o yá+ nǹkan. 13 Orí ni Jèhófà máa fi ọ́ ṣe, kò ní fi ọ́ ṣe ìrù; òkè+ lo máa wà, o ò ní sí nísàlẹ̀, tí o bá ń ṣègbọràn sí àwọn àṣẹ Jèhófà Ọlọ́run rẹ tí mò ń pa fún ọ lónìí pé kí o máa pa mọ́ kí o sì máa tẹ̀ lé. 14 Ẹ ò gbọ́dọ̀ yà kúrò nínú gbogbo ọ̀rọ̀ tí mò ń pa láṣẹ fún yín lónìí, ì báà jẹ́ sí ọ̀tún tàbí sí òsì,+ kí ẹ lè tẹ̀ lé àwọn ọlọ́run míì, kí ẹ sì sìn wọ́n.+
15 “Àmọ́ tí o ò bá pa gbogbo àṣẹ àti òfin Jèhófà Ọlọ́run rẹ mọ́, èyí tí mò ń pa láṣẹ fún ọ lónìí, láti fi hàn pé ò ń fetí sí ohùn rẹ̀, gbogbo ègún yìí máa wá sórí rẹ, ó sì máa bá ọ:+
16 “Ègún máa wà lórí rẹ nínú ìlú, ègún sì máa wà lórí rẹ nínú oko.+
17 “Ègún máa wà lórí apẹ̀rẹ̀+ rẹ àti lórí abọ́ tí o fi ń po nǹkan.+
18 “Ègún máa wà lórí àwọn ọmọ*+ rẹ, èso ilẹ̀ rẹ, ọmọ màlúù àti àgùntàn+ rẹ.
19 “Ègún máa wà lórí rẹ tí o bá wọlé, ègún sì máa wà lórí rẹ tí o bá jáde.
20 “Jèhófà máa mú kí ègún bá ọ, kí nǹkan dà rú fún ọ, kí ìyà sì jẹ ọ́ nínú gbogbo ohun tí o bá dáwọ́ lé títí o fi máa pa run, tí o sì máa yára ṣègbé, torí ìwà búburú tí ò ń hù àti torí pé o pa mí tì.+ 21 Jèhófà máa mú kí àrùn ṣe ọ́ títí ó fi máa pa ọ́ run ní ilẹ̀ tí o fẹ́ lọ gbà.+ 22 Jèhófà máa fi ikọ́ ẹ̀gbẹ kọ lù ọ́, pẹ̀lú akọ ibà,+ ara wíwú, ara gbígbóná, idà,+ ooru tó ń jó nǹkan gbẹ àti èbíbu;+ wọ́n á sì bá ọ títí o fi máa ṣègbé. 23 Ojú ọ̀run tó wà lókè orí rẹ máa di bàbà, ilẹ̀ tó sì wà lábẹ́ ẹsẹ̀ rẹ máa di irin.+ 24 Jèhófà máa sọ òjò ilẹ̀ rẹ di nǹkan lẹ́búlẹ́bú àti eruku tí á máa kù sórí rẹ láti ọ̀run títí o fi máa pa run. 25 Jèhófà máa mú kí àwọn ọ̀tá+ rẹ ṣẹ́gun rẹ. Ọ̀nà kan lo máa gbà yọ sí wọn láti bá wọn jà, àmọ́ ọ̀nà méje ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ lo máa gbà sá kúrò lọ́dọ̀ wọn; o sì máa di ohun àríbẹ̀rù fún gbogbo ìjọba+ ayé. 26 Òkú rẹ á di oúnjẹ fún gbogbo ẹyẹ ojú ọ̀run àtàwọn ẹranko orí ilẹ̀, láìsí ẹnikẹ́ni tó máa lé wọn dà nù.+
27 “Jèhófà máa fi eéwo ilẹ̀ Íjíbítì kọ lù yín, pẹ̀lú jẹ̀díjẹ̀dí, ifo àti àwúfọ́, èyí tí kò ní ṣeé wò sàn. 28 Jèhófà máa mú kí o ya wèrè, kí o fọ́jú,+ kí nǹkan sì dà rú fún ọ.* 29 Wàá máa táràrà kiri ní ọ̀sán gangan, bí afọ́jú ṣe máa ń táràrà torí ó wà lókùnkùn,+ o ò sì ní ṣàṣeyọrí nínú gbogbo ohun tí o bá ń ṣe; wọ́n á máa lù ọ́ ní jìbìtì, wọ́n á sì máa jà ọ́ lólè léraléra, kò ní sẹ́ni tó máa gbà ọ́ sílẹ̀.+ 30 O máa fẹ́ obìnrin sọ́nà, àmọ́ ọkùnrin míì á fipá bá a lò pọ̀. O máa kọ́ ilé, àmọ́ o ò ní gbé ibẹ̀.+ O máa gbin àjàrà, àmọ́ o ò ní rí i lò.+ 31 Wọ́n á pa akọ màlúù rẹ níṣojú rẹ, àmọ́ o ò ní fi ẹnu kàn án rárá. Wọ́n á jí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ níṣojú rẹ, àmọ́ kò ní pa dà sọ́dọ̀ rẹ. Wọ́n á kó àwọn àgùntàn rẹ fún àwọn ọ̀tá rẹ, àmọ́ ẹnì kankan ò ní gbà ọ́ sílẹ̀. 32 Wọ́n á fún àwọn èèyàn míì+ ní àwọn ọmọkùnrin àtàwọn ọmọbìnrin rẹ níṣojú rẹ, àárò wọn á máa sọ ẹ́ nígbà gbogbo, àmọ́ o ò ní rí nǹkan kan ṣe sí i. 33 Àwọn èèyàn tí o kò mọ̀+ ló máa jẹ èso ilẹ̀ rẹ àti gbogbo iṣẹ́ ọwọ́ rẹ. Wọ́n á máa lù ọ́ ní jìbìtì, wọ́n á sì máa rẹ̀ ọ́ wálẹ̀ nígbà gbogbo. 34 Ohun tí ojú rẹ bá rí máa dà ọ́ lórí rú.
35 “Jèhófà máa fi eéwo tó ń roni lára, tí kò sì ṣeé wò sàn kọ lù ọ́ ní orúnkún àti ẹsẹ̀ rẹ, láti àtẹ́lẹsẹ̀ títí dé àtàrí rẹ. 36 Jèhófà máa lé ìwọ àti ọba tí o bá fi jẹ lórí ara rẹ lọ sí orílẹ̀-èdè tí ìwọ àtàwọn baba ńlá rẹ kò mọ̀,+ o sì máa sin àwọn ọlọ́run míì níbẹ̀, àwọn ọlọ́run tí wọ́n fi igi àti òkúta+ ṣe. 37 O máa di ohun tó ń dẹ́rù bani, ẹni ẹ̀gàn* àti ẹni ẹ̀sín láàárín gbogbo àwọn tí Jèhófà bá lé ọ lọ bá.+
38 “Irúgbìn púpọ̀ lo máa kó lọ sí oko, àmọ́ díẹ̀+ lo máa rí kó jọ, torí pé eéṣú máa jẹ ẹ́ run. 39 O máa gbin àjàrà, o sì máa roko rẹ̀, àmọ́ o ò ní rí wáìnì mu, o ò sì ní rí nǹkan kan+ kó jọ, torí kòkòrò mùkúlú ló máa jẹ ẹ́. 40 Igi ólífì máa wà ní gbogbo ilẹ̀ rẹ, àmọ́ o ò ní rí òróró fi para, torí pé àwọn ólífì rẹ máa rẹ̀ dà nù. 41 O máa bí ọmọ lọ́kùnrin àti lóbìnrin, àmọ́ wọn ò ní jẹ́ tìẹ mọ́, torí wọ́n máa kó wọn lẹ́rú.+ 42 Ọ̀wọ́ àwọn kòkòrò* máa bo gbogbo igi àtàwọn èso ilẹ̀ rẹ. 43 Ọwọ́ àjèjì tó wà láàárín rẹ á máa ròkè ju tìẹ lọ ṣáá, àmọ́ ṣe ni ìwọ á máa rẹlẹ̀ sí i. 44 Ó máa yá ọ ní nǹkan, àmọ́ ìwọ ò ní yá a+ ní ohunkóhun. Òun ló máa di orí, ìwọ á sì di ìrù.+
45 “Ó dájú pé gbogbo ègún+ yìí máa wá sórí rẹ, ó máa tẹ̀ lé ọ, ó sì máa bá ọ, títí o fi máa pa run,+ torí pé o ò tẹ̀ lé àṣẹ àti òfin Jèhófà Ọlọ́run rẹ tó pa láṣẹ+ fún ọ, láti fi hàn pé ò ń fetí sí ohùn rẹ̀. 46 Kò ní kúrò lórí ìwọ àti àwọn ọmọ rẹ, ó máa jẹ́ àmì àti ìkìlọ̀+ tó máa wà títí láé, 47 torí o ò fi ìdùnnú àti ayọ̀ tó wá látọkàn sin Jèhófà Ọlọ́run rẹ nígbà tí o ní ohun gbogbo ní ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ.+ 48 Jèhófà máa mú kí àwọn ọ̀tá rẹ dìde sí ọ, o sì máa sìn+ wọ́n tòun ti ebi+ àti òùngbẹ, láìsí aṣọ gidi lọ́rùn rẹ àti láìní ohunkóhun. Ó máa fi àjàgà irin sí ọ lọ́rùn títí ó fi máa pa ọ́ run.
49 “Jèhófà máa gbé orílẹ̀-èdè kan tó wà lọ́nà jíjìn+ dìde sí ọ, láti ìkángun ayé; ó máa kì ọ́ mọ́lẹ̀ bí ẹyẹ idì+ ṣe ń ṣe, orílẹ̀-èdè tí o ò ní gbọ́+ èdè rẹ̀, 50 orílẹ̀-èdè tí ojú rẹ̀ le gan-an, tí kò ní wo ojú arúgbó, tí kò sì ní ṣojúure sí àwọn ọmọdé.+ 51 Wọ́n á jẹ àwọn ọmọ ẹran ọ̀sìn rẹ àti èso ilẹ̀ rẹ títí wọ́n fi máa pa ọ́ run. Wọn ò ní ṣẹ́ ọkà kankan kù fún ọ àti wáìnì tàbí òróró tuntun, ọmọ màlúù tàbí àgùntàn, títí wọ́n fi máa pa ọ́ run.+ 52 Wọ́n máa dó tì ọ́, wọ́n máa sé ọ mọ́ inú gbogbo ìlú* rẹ, jákèjádò ilẹ̀ rẹ títí àwọn ògiri rẹ tó ga, tí o fi ṣe odi tí o gbẹ́kẹ̀ lé fi máa wó lulẹ̀. Àní ó dájú pé wọ́n máa dó tì ọ́ nínú gbogbo ìlú rẹ jákèjádò ilẹ̀ rẹ tí Jèhófà Ọlọ́run rẹ fún ọ.+ 53 O sì máa wá jẹ àwọn ọmọ* rẹ, ẹran ara àwọn ọmọ rẹ lọ́kùnrin àti lóbìnrin+ tí Jèhófà Ọlọ́run rẹ fún ọ, torí bí nǹkan ṣe máa le tó nígbà tí wọ́n bá dó tì ọ́ àti torí wàhálà tí àwọn ọ̀tá rẹ máa kó bá ọ.
54 “Ọkùnrin tí kò lágbaja rárá, tó sì lójú àánú láàárín rẹ kò tiẹ̀ ní ṣàánú arákùnrin rẹ̀ tàbí ìyàwó rẹ̀ tó fẹ́ràn tàbí àwọn ọmọ rẹ̀ tó ṣẹ́ kù, 55 kò sì ní fún wọn ní ìkankan lára ẹran ara àwọn ọmọ rẹ̀ tó máa jẹ, torí kò ní nǹkan kan mọ́ nítorí bí àwọn ọ̀tá ṣe dó tì ọ́ àti bí wàhálà tí wọ́n kó bá àwọn ìlú+ rẹ ṣe pọ̀ tó. 56 Obìnrin tí kò lágbaja tó sì lójú àánú láàárín rẹ, tí kò tiẹ̀ ní ronú rárá láti fi àtẹ́lẹsẹ̀ rẹ̀ kanlẹ̀ torí pé kò lágbaja+ kò ní ṣàánú ọkọ rẹ̀ tó fẹ́ràn tàbí ọmọkùnrin rẹ̀ tàbí ọmọbìnrin rẹ̀, 57 àní kò ní ṣàánú àwọn ohun tó jáde láàárín ẹsẹ̀ rẹ̀ méjèèjì lẹ́yìn tó bímọ àtàwọn ọmọ tó bí. Ó máa jẹ wọ́n níkọ̀kọ̀ torí bí nǹkan ṣe máa le nígbà tí wọ́n bá dó tì ọ́ àti wàhálà tí àwọn ọ̀tá rẹ máa kó bá àwọn ìlú rẹ.
58 “Tí o ò bá rí i pé o tẹ̀ lé gbogbo ọ̀rọ̀ Òfin tí wọ́n kọ sínú ìwé+ yìí, tí o ò sì bẹ̀rù orúkọ+ ológo, tó ń bani lẹ́rù yìí tí Jèhófà+ Ọlọ́run rẹ ní, 59 Jèhófà máa mú kí àwọn àrùn tó le gan-an ṣe ìwọ àti ọmọ rẹ, àwọn ìyọnu+ tó lágbára gan-an tí kò sì ní lọ bọ̀rọ̀, pẹ̀lú àwọn àìsàn tó le gan-an tí kò sì ní lọ bọ̀rọ̀. 60 Ó máa mú gbogbo àìsàn Íjíbítì tí ò ń bẹ̀rù pa dà wá sórí rẹ, ó sì dájú pé wọn ò ní fi ọ́ sílẹ̀. 61 Yàtọ̀ síyẹn, Jèhófà tún máa mú gbogbo àìsàn tàbí àrùn tí wọn ò kọ sínú ìwé Òfin yìí wá sórí rẹ títí o fi máa pa run. 62 Bó tiẹ̀ jẹ́ pé o ti pọ̀ rẹpẹtẹ bí ìràwọ̀ ojú ọ̀run,+ ìwọ̀nba ló máa ṣẹ́ kù+ lára rẹ, torí pé o ò fetí sí ohùn Jèhófà Ọlọ́run rẹ.
63 “Bí inú Jèhófà ṣe dùn nígbà kan láti mú kí nǹkan máa lọ dáadáa fún yín, kí ẹ sì pọ̀ rẹpẹtẹ, bẹ́ẹ̀ náà ni inú Jèhófà ṣe máa dùn láti pa yín run kó sì pa yín rẹ́; ẹ sì máa pa run kúrò ní ilẹ̀ tí ẹ fẹ́ lọ gbà.
64 “Jèhófà máa tú ọ ká sáàárín gbogbo orílẹ̀-èdè, láti ìkángun kan ayé dé ìkángun kejì ayé,+ o sì máa ní láti sin àwọn ọlọ́run tí wọ́n fi igi àti òkúta ṣe níbẹ̀, àwọn ọlọ́run tí ìwọ àtàwọn baba ńlá rẹ kò mọ̀.+ 65 Ọkàn rẹ ò ní balẹ̀ láàárín àwọn orílẹ̀-èdè+ yẹn, àtẹ́lẹsẹ̀ rẹ ò sì ní rí ibi ìsinmi. Dípò ìyẹn, Jèhófà máa mú kí o kó ọkàn sókè,+ ojú rẹ á di bàìbàì, ìrẹ̀wẹ̀sì*+ á sì bá ọ níbẹ̀. 66 Ẹ̀mí rẹ máa wà nínú ewu ńlá, ẹ̀rù á máa bà ọ́ tọ̀sántòru, kò sì ní dá ọ lójú pé wàá rí ìgbàlà. 67 Ní àárọ̀, wàá sọ pé, ‘Ì bá dáa ká ní alẹ́ la wà!’ tó bá sì di alẹ́, wàá sọ pé, ‘Ì bá dáa ká ní àárọ̀ la wà!’ nítorí ìpayà tó máa bá ọkàn rẹ àti nítorí ohun tí ojú rẹ máa rí. 68 Ó dájú pé Jèhófà máa fi ọkọ̀ ojú omi gbé ọ pa dà wá sí Íjíbítì, ní ọ̀nà tí mo sọ fún ọ pé, ‘O ò ní rí i mọ́ láé,’ ẹ sì máa fẹ́ ta ara yín níbẹ̀ fún àwọn ọ̀tá yín pé kí wọ́n fi yín ṣe ẹrúkùnrin àti ẹrúbìnrin, àmọ́ kò ní sẹ́ni tó máa rà yín.”
29 Èyí ni àwọn ọ̀rọ̀ májẹ̀mú tí Jèhófà pa láṣẹ fún Mósè pé kó bá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì dá ní ilẹ̀ Móábù, yàtọ̀ sí májẹ̀mú tó bá wọn dá ní Hórébù.+
2 Mósè pe gbogbo Ísírẹ́lì jọ, ó sì sọ fún wọn pé: “Ẹ ti rí gbogbo ohun tí Jèhófà ṣe níṣojú yín ní ilẹ̀ Íjíbítì sí Fáráò àti gbogbo ìránṣẹ́ rẹ̀ àti gbogbo ilẹ̀ rẹ̀,+ 3 àwọn ìdájọ́* tó rinlẹ̀ tí ẹ fojú rí, àwọn iṣẹ́ àmì àti iṣẹ́ ìyanu ńlá yẹn.+ 4 Àmọ́ títí di òní yìí, Jèhófà kò tíì fún yín ní ọkàn láti lóyè, ojú láti rí àti etí láti gbọ́.+ 5 ‘Bí mo ṣe darí yín jálẹ̀ ogójì (40) ọdún nínú aginjù,+ aṣọ yín ò gbó mọ́ yín lára, bàtà yín ò sì gbó mọ́ yín lẹ́sẹ̀.+ 6 Ẹ ò jẹ búrẹ́dì, ẹ ò sì mu wáìnì tàbí ohunkóhun míì tó ní ọtí, kí ẹ lè mọ̀ pé èmi ni Jèhófà Ọlọ́run yín.’ 7 Nígbà tí ẹ wá dé ibí yìí, Síhónì ọba Hẹ́ṣíbónì+ àti Ógù ọba Báṣánì+ jáde wá bá wa jagun, àmọ́ a ṣẹ́gun wọn.+ 8 Lẹ́yìn náà, a gba ilẹ̀ wọn, a sì fún àwọn ọmọ Rúbẹ́nì, àwọn ọmọ Gádì àti ààbọ̀ ẹ̀yà àwọn ọmọ Mánásè+ pé kó jẹ́ ogún tiwọn. 9 Torí náà, ẹ máa pa àwọn ọ̀rọ̀ májẹ̀mú yìí mọ́, kí ẹ sì máa tẹ̀ lé wọn, kí gbogbo ohun tí ẹ bá ń ṣe lè yọrí sí rere.+
10 “Gbogbo yín lẹ dúró níwájú Jèhófà Ọlọ́run yín lónìí, àwọn olórí ẹ̀yà yín, àwọn àgbààgbà yín, àwọn aṣojú yín, gbogbo ọkùnrin Ísírẹ́lì, 11 àwọn ọmọ yín, àwọn ìyàwó yín,+ àwọn àjèjì tó wà nínú ibùdó yín,+ látorí ẹni tó ń bá yín ṣẹ́gi dórí ẹni tó ń bá yín fa omi. 12 Torí kí ẹ lè wọnú májẹ̀mú Jèhófà Ọlọ́run yín àti ìbúra rẹ̀, èyí tí Jèhófà Ọlọ́run yín ń bá yín dá lónìí lẹ ṣe wà níbí,+ 13 kó bàa lè fìdí rẹ̀ múlẹ̀ lónìí pé èèyàn òun lẹ jẹ́,+ kó sì jẹ́ Ọlọ́run yín,+ bó ṣe ṣèlérí fún yín gẹ́lẹ́, bó sì ṣe búra fún àwọn baba ńlá yín, Ábúráhámù,+ Ísákì+ àti Jékọ́bù.+
14 “Ẹ̀yin nìkan kọ́ ni mò ń bá dá májẹ̀mú yìí, tí mo sì ń búra fún, 15 àmọ́ ó tún kan àwọn tó dúró síbí pẹ̀lú wa lónìí, níwájú Jèhófà Ọlọ́run wa àti àwọn tí kò sí níbí pẹ̀lú wa lónìí. 16 (Torí ẹ mọ̀ dáadáa bí a ṣe gbé ní ilẹ̀ Íjíbítì àti bí a ṣe gba àárín oríṣiríṣi orílẹ̀-èdè kọjá lẹ́nu ìrìn àjò wa.+ 17 Ẹ sì máa ń rí àwọn ohun ìríra wọn àti àwọn òrìṣà ẹ̀gbin*+ wọn, tí wọ́n fi igi, òkúta, fàdákà àti wúrà ṣe, tó wà láàárín wọn.) 18 Ẹ ṣọ́ra, kó má bàa sí ọkùnrin tàbí obìnrin kankan, ìdílé tàbí ẹ̀yà kan láàárín yín lónìí tí ọkàn rẹ̀ máa yí pa dà kúrò lọ́dọ̀ Jèhófà Ọlọ́run wa láti lọ sin àwọn ọlọ́run àwọn orílẹ̀-èdè yẹn,+ kó má bàa sí gbòǹgbò kankan láàárín yín tó ń so èso tó ní májèlé àti iwọ.*+
19 “Àmọ́ tí ẹnì kan bá gbọ́ ọ̀rọ̀ ìbúra yìí, tó sì ń fọ́nnu lọ́kàn ara rẹ̀ pé, ‘Tí mo bá tiẹ̀ fi àáké kọ́rí, tí mò ń ṣe ohun tí ọkàn mi fẹ́, màá ní àlàáfíà,’ gbogbo ohun* tó wà lọ́nà rẹ̀ ló máa pa run, 20 Jèhófà ò ní ṣe tán láti dárí jì í.+ Kàkà bẹ́ẹ̀, Jèhófà máa bínú gidigidi sí ẹni náà, ó dájú pé gbogbo ègún tí wọ́n sì kọ sínú ìwé yìí máa wá sórí rẹ̀,+ ó sì dájú pé Jèhófà máa pa orúkọ rẹ̀ rẹ́ kúrò lábẹ́ ọ̀run. 21 Jèhófà máa wá yọ òun nìkan kúrò nínú gbogbo ẹ̀yà Ísírẹ́lì kí àjálù lè dé bá a, bó ṣe wà nínú gbogbo ègún májẹ̀mú tí wọ́n kọ sínú ìwé Òfin yìí.
22 “Tí ìran àwọn ọmọ yín lọ́jọ́ iwájú àti àwọn àjèjì tó wá láti ọ̀nà jíjìn bá rí àwọn àjálù tó bá ilẹ̀ náà, àwọn ìyọnu tí Jèhófà mú wá sórí rẹ̀, 23 ìyẹn, imí ọjọ́, iyọ̀ àti iná, kí wọ́n má bàa fúnrúgbìn kankan sí gbogbo ilẹ̀ rẹ̀ tàbí kí irúgbìn hù níbẹ̀, kí ewéko kankan má sì hù níbẹ̀, bí ìparun Sódómù àti Gòmórà,+ Ádímà àti Sébóímù,+ tí Jèhófà fi ìbínú àti ìrunú rẹ̀ pa run, 24 àwọn àti gbogbo orílẹ̀-èdè máa sọ pé, ‘Kí nìdí tí Jèhófà fi ṣe báyìí sí ilẹ̀ yìí?+ Kí ló fa ìbínú tó le, tó kàmàmà yìí?’ 25 Wọ́n á wá sọ pé, ‘Torí pé wọ́n pa májẹ̀mú Jèhófà+ Ọlọ́run àwọn baba ńlá wọn tì ni, èyí tó bá wọn dá nígbà tó mú wọn kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì.+ 26 Wọ́n lọ ń sin àwọn ọlọ́run míì, wọ́n sì ń forí balẹ̀ fún wọn, àwọn ọlọ́run tí wọn ò mọ̀, tí kò sì gbà pé kí wọ́n máa jọ́sìn.*+ 27 Jèhófà wá bínú gidigidi sí ilẹ̀ náà, ó sì mú gbogbo ègún tí wọ́n kọ sínú ìwé yìí wá sórí rẹ̀.+ 28 Torí náà, Jèhófà fi ìbínú àti ìrunú àti ìkannú ńlá fà wọ́n tu kúrò ní ilẹ̀ wọn,+ ó sì kó wọn lọ sí ilẹ̀ míì níbi tí wọ́n wà lónìí.’+
29 “Àwọn ohun tó wà ní ìpamọ́ jẹ́ ti Jèhófà Ọlọ́run wa,+ àmọ́ àwọn ohun tí a ṣí payá jẹ́ tiwa àti àwọn àtọmọdọ́mọ wa títí láé, ká lè máa tẹ̀ lé gbogbo ọ̀rọ̀ Òfin yìí.+
30 “Tí gbogbo ọ̀rọ̀ yìí bá ṣẹ sí ọ lára, ìbùkún àti ègún tí mo fi síwájú rẹ,+ tí o sì rántí wọn*+ ní gbogbo orílẹ̀-èdè tí Jèhófà Ọlọ́run rẹ tú ọ+ ká sí, 2 tí o wá pa dà sọ́dọ̀ Jèhófà Ọlọ́run+ rẹ, tí o fi gbogbo ọkàn rẹ àti gbogbo ara*+ rẹ fetí sí ohùn rẹ̀, ìwọ àti àwọn ọmọ rẹ, gẹ́gẹ́ bí gbogbo ohun tí mò ń pa láṣẹ fún ọ lónìí, 3 nígbà náà, Jèhófà Ọlọ́run rẹ máa mú àwọn èèyàn rẹ tí wọ́n kó lẹ́rú+ pa dà wá, ó máa ṣàánú+ rẹ, ó sì máa kó ọ jọ látọ̀dọ̀ gbogbo èèyàn tí Jèhófà Ọlọ́run rẹ tú ọ+ ká sí. 4 Ì báà jẹ́ ìpẹ̀kun ọ̀run ni àwọn èèyàn rẹ tú ká sí, Jèhófà Ọlọ́run rẹ máa kó ọ jọ, á sì mú ọ pa dà wá + láti ibẹ̀. 5 Jèhófà Ọlọ́run rẹ máa mú ọ wá sí ilẹ̀ tí àwọn bàbá rẹ gbà, ó sì máa di tìẹ; á mú kí nǹkan máa lọ dáadáa fún ọ, á sì mú kí o pọ̀ ju àwọn bàbá+ rẹ. 6 Jèhófà Ọlọ́run rẹ máa wẹ ọkàn rẹ mọ́* àti ọkàn ọmọ+ rẹ, kí o lè fi gbogbo ọkàn rẹ àti gbogbo ara* rẹ nífẹ̀ẹ́ Jèhófà Ọlọ́run rẹ, kí o sì máa wà láàyè.+ 7 Jèhófà Ọlọ́run rẹ máa mú gbogbo ègún yìí wá sórí àwọn ọ̀tá rẹ, tí wọ́n kórìíra rẹ tí wọ́n sì ṣe inúnibíni sí ọ.+
8 “Nígbà náà, wàá pa dà, wàá fetí sí ohùn Jèhófà, wàá sì pa gbogbo àṣẹ rẹ̀ tí mò ń pa fún ọ lónìí mọ́. 9 Jèhófà Ọlọ́run rẹ máa bù kún gbogbo iṣẹ́ ọwọ́+ rẹ lọ́pọ̀lọpọ̀, ó máa mú kí àwọn ọmọ rẹ, àwọn ẹran ọ̀sìn rẹ àti èso ilẹ̀ rẹ di púpọ̀, torí pé lẹ́ẹ̀kan sí i inú Jèhófà máa dùn láti mú kí nǹkan lọ dáadáa fún ọ bí inú rẹ̀ ṣe dùn sí àwọn baba ńlá+ rẹ. 10 Nígbà yẹn, wàá fetí sí ohùn Jèhófà Ọlọ́run rẹ, wàá sì pa àwọn àṣẹ rẹ̀ mọ́ àti àwọn òfin rẹ̀ tí wọ́n kọ sínú ìwé Òfin yìí, wàá sì fi gbogbo ọkàn rẹ àti gbogbo ara*+ rẹ pa dà sọ́dọ̀ Jèhófà Ọlọ́run rẹ.
11 “Àṣẹ tí mò ń pa fún ọ lónìí yìí kò nira jù fún ọ, kì í sì í ṣe ohun tí kò sí lárọ̀ọ́wọ́tó+ rẹ.* 12 Kò sí ní ọ̀run, débi tí wàá fi sọ pé, ‘Ta ló máa lọ bá wa mú un wá ní ọ̀run, ká lè gbọ́ ọ, ká sì máa tẹ̀ lé e?’+ 13 Bẹ́ẹ̀ ni kò sí ní òdìkejì òkun, débi tí wàá fi sọ pé, ‘Ta ló máa sọdá lọ sí òdìkejì òkun kó lè bá wa mú un wá, ká lè gbọ́ ọ, ká sì máa tẹ̀ lé e?’ 14 Àmọ́ tòsí rẹ gan-an ni ọ̀rọ̀ náà wà, ní ẹnu rẹ àti ní ọkàn+ rẹ, kí o lè máa ṣe é.+
15 “Wò ó, mo fi ìyè àti ire, ikú àti ibi+ sí iwájú rẹ lónìí. 16 Tí o bá fetí sí àṣẹ Jèhófà Ọlọ́run rẹ tí mò ń pa fún ọ lónìí, tí ò ń nífẹ̀ẹ́ Jèhófà Ọlọ́run+ rẹ, tí ò ń rìn ní àwọn ọ̀nà rẹ̀, tí o sì ń pa àwọn àṣẹ rẹ̀ mọ́ àti àwọn òfin rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ìdájọ́ rẹ̀, wàá máa wà láàyè,+ wàá sì máa pọ̀ sí i, Jèhófà Ọlọ́run rẹ sì máa bù kún ọ ní ilẹ̀ tí o fẹ́ lọ gbà.+
17 “Àmọ́ tí ọkàn yín bá yí pa dà,+ tí ẹ ò fetí sílẹ̀, tí ẹ sì jẹ́ kí ọkàn yín fà sí àwọn ọlọ́run míì, tí ẹ wá ń forí balẹ̀ fún wọn, tí ẹ sì ń sìn wọ́n,+ 18 mò ń sọ fún yín lónìí pé ó dájú pé ẹ máa ṣègbé.+ Ẹ̀mí yín ò sì ní gùn lórí ilẹ̀ tí ẹ̀ ń sọdá Jọ́dánì lọ gbà. 19 Mò ń fi ọ̀run àti ayé ṣe ẹlẹ́rìí lòdì sí ọ lónìí, pé mo ti fi ìyè àti ikú sí iwájú rẹ, ìbùkún àti ègún;+ yan ìyè, kí o lè máa wà láàyè,+ ìwọ àti àwọn àtọmọdọ́mọ+ rẹ, 20 nípa nínífẹ̀ẹ́ Jèhófà Ọlọ́run+ rẹ, kí o máa fetí sí ohùn rẹ̀, kí o sì rọ̀ mọ́ ọn,+ torí òun ni ìyè rẹ, òun ló sì máa mú kí o pẹ́ lórí ilẹ̀ tí Jèhófà búra pé òun máa fún àwọn baba ńlá rẹ Ábúráhámù, Ísákì àti Jékọ́bù.”+
31 Lẹ́yìn náà, Mósè jáde lọ sọ àwọn ọ̀rọ̀ yìí fún gbogbo Ísírẹ́lì, 2 ó sọ fún wọn pé: “Ẹni ọgọ́fà (120) ọdún ni mí lónìí.+ Mi ò lè darí yín mọ́,* torí Jèhófà ti sọ fún mi pé, ‘O ò ní sọdá Jọ́dánì yìí.’+ 3 Jèhófà Ọlọ́run rẹ ló máa sọdá ṣáájú rẹ, òun fúnra rẹ̀ máa pa àwọn orílẹ̀-èdè yìí run kúrò níwájú rẹ, wàá sì lé wọn kúrò.+ Jóṣúà ló máa kó yín sọdá,+ bí Jèhófà ṣe sọ gẹ́lẹ́. 4 Ohun tí Jèhófà ṣe sí Síhónì+ àti Ógù,+ àwọn ọba Ámórì àti sí ilẹ̀ wọn, nígbà tó pa wọ́n run ló máa ṣe sí wọn gẹ́lẹ́.+ 5 Jèhófà máa bá yín ṣẹ́gun wọn, gbogbo ohun tí mo sì pa láṣẹ fún yín ni kí ẹ ṣe sí wọn gẹ́lẹ́.+ 6 Ẹ jẹ́ onígboyà àti alágbára.+ Ẹ má bẹ̀rù, ẹ má sì gbọ̀n rìrì níwájú wọn,+ torí Jèhófà Ọlọ́run yín ló ń bá yín lọ. Kò ní pa yín tì, kò sì ní fi yín sílẹ̀.”+
7 Mósè wá pe Jóṣúà, ó sì sọ fún un níṣojú gbogbo Ísírẹ́lì pé: “Jẹ́ onígboyà àti alágbára,+ torí ìwọ lo máa mú àwọn èèyàn yìí wọ ilẹ̀ tí Jèhófà búra fún àwọn baba ńlá wọn pé òun máa fún wọn, wàá sì fún wọn kí wọ́n lè jogún rẹ̀.+ 8 Jèhófà ló ń lọ níwájú rẹ, ó sì máa wà pẹ̀lú rẹ.+ Kò ní pa ọ́ tì, kò sì ní fi ọ́ sílẹ̀. Má bẹ̀rù, má sì jáyà.”+
9 Mósè wá kọ Òfin yìí,+ ó sì fún àwọn àlùfáà, àwọn ọmọ Léfì, tí wọ́n ń gbé àpótí májẹ̀mú Jèhófà àti gbogbo àgbààgbà Ísírẹ́lì. 10 Mósè pàṣẹ fún wọn pé: “Ní òpin ọdún méje-méje, ní àkókò rẹ̀ nígbà ọdún ìtúsílẹ̀,+ ní àkókò Àjọyọ̀ Àtíbàbà,+ 11 nígbà tí gbogbo Ísírẹ́lì bá wá síwájú Jèhófà+ Ọlọ́run rẹ ní ibi tó yàn, kí ẹ ka Òfin yìí sí gbogbo Ísírẹ́lì létí.+ 12 Ẹ kó àwọn èèyàn náà jọ,+ àwọn ọkùnrin, àwọn obìnrin, àwọn ọmọdé* àti àwọn àjèjì yín tó ń gbé nínú àwọn ìlú* yín, kí wọ́n lè fetí sílẹ̀, kí wọ́n sì kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà Ọlọ́run yín, kí wọ́n máa bẹ̀rù rẹ̀, kí wọ́n sì lè máa rí i dájú pé àwọn ń tẹ̀ lé gbogbo ọ̀rọ̀ Òfin yìí. 13 Àwọn ọmọ wọn tí kò tíì mọ Òfin yìí á wá fetí sílẹ̀,+ wọ́n á sì kọ́ láti máa bẹ̀rù Jèhófà Ọlọ́run yín ní gbogbo ọjọ́ tí ẹ bá fi wà lórí ilẹ̀ tí ẹ̀ ń sọdá Jọ́dánì lọ gbà.”+
14 Lẹ́yìn náà, Jèhófà sọ fún Mósè pé: “Wò ó! Ọjọ́ ikú rẹ ti sún mọ́lé.+ Pe Jóṣúà, kí ẹ sì lọ síwájú* àgọ́ ìpàdé, kí n lè faṣẹ́ lé e lọ́wọ́.”+ Mósè àti Jóṣúà wá lọ síwájú àgọ́ ìpàdé. 15 Jèhófà wá fara hàn ní àgọ́ náà nínú ọwọ̀n ìkùukùu,* ọwọ̀n ìkùukùu náà sì dúró ní ẹnu ọ̀nà àgọ́ náà.+
16 Jèhófà sọ fún Mósè pé: “Wò ó! O ò ní pẹ́ kú,* àwọn èèyàn yìí á sì bẹ̀rẹ̀ sí í bá àwọn ọlọ́run àjèjì tó yí wọn ká ní ilẹ̀ tí wọ́n ń lọ ṣe àgbèrè ẹ̀sìn.+ Wọ́n á pa mí tì,+ wọ́n á sì da májẹ̀mú mi tí mo bá wọn dá.+ 17 Màá bínú sí wọn gidigidi nígbà yẹn,+ màá pa wọ́n tì,+ màá sì fi ojú mi pa mọ́ fún wọn+ títí wọ́n á fi pa run. Tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àjálù àti wàhálà bá wá dé bá wọn,+ wọ́n á sọ pé, ‘Ṣebí torí Ọlọ́run wa ò sí láàárín wa ni àjálù yìí ṣe dé bá wa?’+ 18 Àmọ́ màá fi ojú mi pa mọ́ fún wọn lọ́jọ́ yẹn torí gbogbo ìwà ibi tí wọ́n hù, tí wọ́n lọ ń tọ àwọn ọlọ́run míì lẹ́yìn.+
19 “Ẹ kọ ọ̀rọ̀ orin yìí sílẹ̀ fún ara yín,+ kí ẹ sì fi kọ́ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.+ Ẹ fi kọ́ wọn,* kí orin yìí lè ṣe ẹlẹ́rìí mi lòdì sí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.+ 20 Tí mo bá mú wọn dé ilẹ̀ tí mo búra nípa rẹ̀ fún àwọn baba ńlá wọn,+ ilẹ̀ tí wàrà àti oyin ti ń ṣàn,+ tí wọ́n jẹun tẹ́rùn, tí nǹkan sì ń lọ dáadáa fún wọn,*+ wọ́n á lọ máa tọ àwọn ọlọ́run míì lẹ́yìn, wọ́n á sì máa sìn wọ́n, wọ́n á hùwà àfojúdi sí mi, wọ́n á sì da májẹ̀mú mi.+ 21 Tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àjálù àti wàhálà bá dé bá wọn,+ orin yìí máa jẹ́ ẹlẹ́rìí fún wọn, (torí àwọn àtọmọdọ́mọ wọn ò gbọ́dọ̀ gbàgbé rẹ̀), torí mo ti mọ ohun tí wọ́n ń rò lọ́kàn+ kí n tiẹ̀ tó mú wọn dé ilẹ̀ tí mo búra nípa rẹ̀.”
22 Mósè wá kọ ọ̀rọ̀ orin yìí sílẹ̀ ní ọjọ́ yẹn, ó sì fi kọ́ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.
23 Lẹ́yìn náà, Ó* fa iṣẹ́ lé Jóṣúà+ ọmọ Núnì lọ́wọ́, ó sọ pé: “Jẹ́ onígboyà àti alágbára,+ torí ìwọ lo máa mú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì wọ ilẹ̀ tí mo búra fún wọn nípa rẹ̀,+ mi ò sì ní fi ọ́ sílẹ̀.”
24 Gbàrà tí Mósè kọ gbogbo ọ̀rọ̀ Òfin yìí sínú ìwé tán,+ 25 Mósè pàṣẹ fún àwọn ọmọ Léfì tó ń gbé àpótí májẹ̀mú Jèhófà, pé: 26 “Ẹ gba ìwé Òfin yìí,+ kí ẹ fi sí ẹ̀gbẹ́ àpótí+ májẹ̀mú Jèhófà Ọlọ́run yín, kó sì jẹ́ ẹlẹ́rìí lòdì sí yín níbẹ̀. 27 Torí mo mọ̀ dáadáa pé ọlọ̀tẹ̀ ni yín,+ ẹ sì lágídí.*+ Tí ẹ bá ń ṣọ̀tẹ̀ sí Jèhófà tó báyìí nígbà tí mo ṣì wà láàyè pẹ̀lú yín, tí mo bá wá kú ńkọ́! 28 Ẹ kó gbogbo àgbààgbà ẹ̀yà yín àti àwọn olórí yín jọ sọ́dọ̀ mi, kí n lè fi àwọn ọ̀rọ̀ yìí tó wọn létí, kí n sì fi ọ̀run àti ayé ṣe ẹlẹ́rìí lòdì sí wọn.+ 29 Torí mo mọ̀ dáadáa pé tí mo bá ti kú, ó dájú pé ẹ máa ṣe ohun tó burú,+ ẹ sì máa yà kúrò lójú ọ̀nà tí mo pa láṣẹ fún yín. Ó dájú pé àjálù máa dé bá yín+ nígbẹ̀yìn ọjọ́, torí ẹ máa ṣe ohun tó burú lójú Jèhófà, iṣẹ́ ọwọ́ yín sì máa múnú bí i.”
30 Mósè wá ka àwọn ọ̀rọ̀ orin yìí sí gbogbo ìjọ Ísírẹ́lì létí, láti ìbẹ̀rẹ̀ dé ìparí:+
32 “Ẹ fetí sílẹ̀, ẹ̀yin ọ̀run, màá sì sọ̀rọ̀;
Kí ayé sì gbọ́ ọ̀rọ̀ ẹnu mi.
2 Ìtọ́ni mi máa rọ̀ bí òjò;
Ọ̀rọ̀ mi á sì sẹ̀ bí ìrì,
Bí òjò winniwinni sórí koríko
Àti ọ̀wààrà òjò sórí ewéko.
3 Torí màá kéde orúkọ Jèhófà.+
Ẹ sọ bí Ọlọ́run+ wa ṣe tóbi tó!
5 Àwọn ló hùwà ìbàjẹ́.+
Wọn kì í ṣe ọmọ rẹ̀, àwọn ló kan àbùkù.+
Ìran alárèékérekè àti oníbékebèke ni wọ́n!+
Ṣebí òun ni Bàbá yín tó mú kí ẹ wà,+
Ẹni tó dá yín, tó sì fìdí yín múlẹ̀ gbọn-in?
7 Ẹ rántí ìgbà àtijọ́;
Ẹ ronú nípa ọdún àwọn ìran tó ti kọjá.
Bi bàbá rẹ, á sì sọ fún ọ;+
Bi àwọn àgbààgbà rẹ, wọ́n á sì jẹ́ kí o mọ̀.
8 Nígbà tí Ẹni Gíga Jù Lọ fún àwọn orílẹ̀-èdè ní ogún+ wọn,
Nígbà tó ya àwọn ọmọ Ádámù* sọ́tọ̀ọ̀tọ̀,+
Ó pààlà fún àwọn èèyàn+
Gẹ́gẹ́ bí iye àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.+
11 Bí ẹyẹ idì ṣe ń ru ìtẹ́ rẹ̀ sókè,
Tó ń rá bàbà lórí àwọn ọmọ rẹ̀ tó ṣẹ̀ṣẹ̀ gúnyẹ̀ẹ́,
Tó ń na àwọn ìyẹ́ rẹ̀ jáde láti fi gbé wọn,
Tó ń gbé wọn sórí apá+ rẹ̀,
12 Jèhófà nìkan ló ń darí rẹ̀;*+
Kò sí ọlọ́run àjèjì kankan pẹ̀lú rẹ̀.+
Ó fi oyin inú àpáta bọ́ ọ
Àti òróró látinú akọ àpáta,
14 Bọ́tà ọ̀wọ́ ẹran àti wàrà agbo ẹran,
Pẹ̀lú àgùntàn tó dáa jù,*
Àwọn àgbò Báṣánì àti àwọn òbúkọ,
O sì mu wáìnì tó tinú ẹ̀jẹ̀* èso àjàrà jáde.
15 Nígbà tí Jéṣúrúnì* sanra tán, ó di ọlọ̀tẹ̀, ó sì ń tàpá.
O ti sanra, o ti ki, o sì ti kún.+
Ó wá pa Ọlọ́run tì, ẹni tó dá a,+
Ó sì fojú àbùkù wo Àpáta ìgbàlà rẹ̀.
17 Àwọn ẹ̀mí èṣù ni wọ́n rúbọ sí, kì í ṣe Ọlọ́run,+
Wọ́n ń rúbọ sí àwọn ọlọ́run tí wọn ò mọ̀,
Àwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ dé lẹ́nu àìpẹ́ yìí,
Sí àwọn ọlọ́run tí àwọn baba ńlá yín ò mọ̀.
19 Nígbà tí Jèhófà rí i, ó kọ̀ wọ́n,+
Torí àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ àtàwọn ọmọbìnrin rẹ̀ ṣẹ̀ ẹ́.
20 Ó wá sọ pé, ‘Màá fojú pa mọ́ fún wọn;+
Màá wo ohun tó máa gbẹ̀yìn wọn.
21 Wọ́n ti fi ohun tí kì í ṣe ọlọ́run+ mú mi bínú;*
Wọ́n ti fi àwọn òrìṣà+ wọn tí kò ní láárí múnú bí mi.
23 Màá fi kún àwọn ìyọnu wọn;
Màá sì ta gbogbo ọfà mi lù wọ́n.
Màá rán eyín àwọn ẹranko sí wọn,+
Àti oró àwọn ẹran tó ń fàyà fà lórí ilẹ̀.
25 Ní ìta, idà máa mú kí ọ̀fọ̀ ṣẹ̀ wọ́n;+
Nínú ilé, jìnnìjìnnì+ á bò wọ́n,
Ọ̀dọ́kùnrin àti wúńdíá,
Ọmọ ọwọ́ àti ẹni tó ní ewú lórí.+
26 Ǹ bá sọ pé: “Màá tú wọn ká;
Màá mú kí àwọn èèyàn gbàgbé wọn,”
27 Tí kì í bá ṣe pé mò ń bẹ̀rù ohun tí ọ̀tá máa ṣe,+
Torí àwọn elénìní lè túmọ̀ rẹ̀ sí nǹkan míì.+
Wọ́n lè sọ pé: “Ọwọ́ wa ti mókè;+
Jèhófà kọ́ ló ṣe gbogbo èyí.”
29 Ká sọ pé wọ́n gbọ́n ni!+ Wọn ì bá ro ọ̀rọ̀ yìí dáadáa.+
Kí wọ́n ro ibi tó máa já sí.+
30 Báwo ni ẹnì kan ṣe lè lé ẹgbẹ̀rún kan (1,000),
Kí ẹni méjì sì mú kí ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá (10,000) sá?+
Tí kì í bá ṣe pé Àpáta wọn ti tà wọ́n,+
Tí Jèhófà sì ti fi wọ́n lé ọ̀tá lọ́wọ́.
32 Torí inú àjàrà Sódómù ni àjàrà wọn ti wá
Àti látinú ilẹ̀ onípele Gòmórà.+
Àwọn èso àjàrà onímájèlé ni èso àjàrà wọn,
Àwọn òṣùṣù wọn korò.+
33 Oró ejò ni wáìnì wọn,
Oró burúkú àwọn ṣèbé.
34 Ṣebí ọ̀dọ̀ mi ni mo tọ́jú rẹ̀ sí,
Tí mo sé e mọ́ ilé ìkẹ́rùsí+ mi?
35 Tèmi ni ẹ̀san àti ìyà ẹ̀ṣẹ̀,+
Ní àkókò náà tí ẹsẹ̀ wọn máa yọ̀ tẹ̀rẹ́,+
Torí ọjọ́ àjálù wọn sún mọ́lé,
Ohun tó sì ń dúró dè wọ́n máa tètè dé.’
36 Torí Jèhófà máa dá ẹjọ́ àwọn èèyàn+ rẹ̀,
Ó sì máa káàánú* àwọn ìránṣẹ́+ rẹ̀,
Tó bá rí i pé okun wọn ti ń tán,
Tó sì rí i pé àwọn tí kò ní olùrànlọ́wọ́ àtàwọn tó ti rẹ̀ ló ṣẹ́ kù.
37 Ó máa wá sọ pé, ‘Àwọn ọlọ́run+ wọn dà,
Àpáta tí wọ́n sá di,
38 Tó máa ń jẹ ọ̀rá àwọn ẹbọ wọn,*
Tó ń mu wáìnì ọrẹ ohun mímu+ wọn?
Jẹ́ kí wọ́n dìde wá ràn yín lọ́wọ́.
Kí wọ́n di ibi ààbò fún yín.
39 Ẹ rí i báyìí pé èmi, àní èmi ni ẹni náà,+
Kò sí ọlọ́run kankan yàtọ̀ sí mi.+
Mo lè pani, mo sì lè sọni di alààyè.+
40 Torí mo gbé ọwọ́ mi sókè sí ọ̀run,
Mo sì búra pé: “Bí mo ti wà láàyè títí láé,”+
41 Tí mo bá pọ́n idà mi tó ń kọ mànà,
Tí mo sì múra ọwọ́ mi sílẹ̀ láti ṣèdájọ́,+
Màá san àwọn ọ̀tá+ mi lẹ́san,
Màá sì fìyà jẹ àwọn tó kórìíra mi.
42 Màá mú kí ọfà mi mu ẹ̀jẹ̀ yó,
Idà mi á sì jẹ ẹran,
Pẹ̀lú ẹ̀jẹ̀ àwọn tí a pa àti àwọn ẹrú,
Pẹ̀lú orí àwọn aṣáájú ọ̀tá.’
43 Ẹ bá àwọn èèyàn+ rẹ̀ yọ̀, ẹ̀yin orílẹ̀-èdè,
Torí ó máa gbẹ̀san ẹ̀jẹ̀ àwọn ìránṣẹ́+ rẹ̀,
Ó máa san àwọn ọ̀tá+ rẹ̀ lẹ́san,
Ó sì máa ṣe ètùtù fún ilẹ̀ àwọn èèyàn rẹ̀.”*
44 Mósè ka gbogbo ọ̀rọ̀ orin yìí sí àwọn èèyàn+ náà létí, òun àti Hóṣéà*+ ọmọ Núnì. 45 Lẹ́yìn tí Mósè bá gbogbo Ísírẹ́lì sọ gbogbo ọ̀rọ̀ yìí tán, 46 ó sọ fún wọn pé: “Ẹ fi gbogbo ọ̀rọ̀ tí mo fi kìlọ̀ fún yín lónìí+ sọ́kàn, kí ẹ lè pàṣẹ fún àwọn ọmọ yín pé, kí wọ́n rí i pé àwọn ń tẹ̀ lé gbogbo ọ̀rọ̀ Òfin+ yìí. 47 Torí èyí kì í ṣe ọ̀rọ̀ tí kò wúlò fún yín, àmọ́ òun ló máa mú kí ẹ wà láàyè,+ ọ̀rọ̀ yìí sì máa mú kí ẹ̀mí yín gùn lórí ilẹ̀ tí ẹ̀ ń sọdá Jọ́dánì lọ gbà.”
48 Jèhófà bá Mósè sọ̀rọ̀ ní ọjọ́ yìí kan náà pé: 49 “Gun òkè Ábárímù+ yìí lọ, Òkè Nébò,+ tó wà ní ilẹ̀ Móábù, tó dojú kọ Jẹ́ríkò, kí o sì wo ilẹ̀ Kénáánì, tí mo fẹ́ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé kó di tiwọn.+ 50 O máa kú sórí òkè tí o fẹ́ gùn yìí, a ó sì kó ọ jọ pẹ̀lú àwọn èèyàn rẹ,* bí Áárónì ẹ̀gbọ́n rẹ ṣe kú sórí Òkè Hóórì+ gẹ́lẹ́, tí wọ́n sì kó o jọ pẹ̀lú àwọn èèyàn rẹ̀, 51 torí pé ẹ̀yin méjèèjì kò jẹ́ olóòótọ́ sí mi láàárín àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, níbi omi Mẹ́ríbà+ ti Kádéṣì ní aginjù Síínì, torí pé ẹ ò fi hàn pé mo jẹ́ mímọ́ lójú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.+ 52 Ọ̀ọ́kán ni wàá ti rí ilẹ̀ náà, àmọ́ o ò ní wọ ilẹ̀ tí mo fẹ́ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.”+
33 Bí Mósè èèyàn Ọlọ́run tòótọ́ ṣe súre fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kó tó kú nìyí.+ 2 Ó sọ pé:
“Jèhófà wá láti Sínáì,+
Ó sì tàn sórí wọn láti Séírì.
Ògo rẹ̀ tàn láti agbègbè olókè Páránì,+
Ọ̀kẹ́ àìmọye* àwọn ẹni mímọ́+ sì wà pẹ̀lú rẹ̀,
Àwọn jagunjagun+ rẹ̀ wà ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀.
7 Ó sì súre fún Júdà+ pé:
“Ìwọ Jèhófà, gbọ́ ohùn Júdà,+
Kí o sì mú un pa dà sọ́dọ̀ àwọn èèyàn rẹ̀.
8 Ó sọ nípa Léfì pé:+
O bẹ̀rẹ̀ sí í bá a fà á lẹ́gbẹ̀ẹ́ omi Mẹ́ríbà,+
9 Ẹni tó sọ nípa bàbá àti ìyá rẹ̀ pé, ‘Mi ò kà wọ́n sí.’
Ó tiẹ̀ tún kọ àwọn arákùnrin rẹ̀,+
Ó sì pa àwọn ọmọ rẹ̀ tì.
Torí wọ́n tẹ̀ lé ọ̀rọ̀ rẹ,
Wọ́n sì pa májẹ̀mú rẹ mọ́.+
11 Bù kún agbára rẹ̀, Jèhófà,
Kí inú rẹ sì dùn sí iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀.
Fọ́ ẹsẹ̀* àwọn tó dìde sí i,
Kí àwọn tó kórìíra rẹ̀ má bàa dìde mọ́.”
12 Ó sọ nípa Bẹ́ńjámínì pé:+
“Kí ẹni ọ̀wọ́n Jèhófà máa gbé láìséwu lọ́dọ̀ rẹ̀;
Bó ṣe ń dáàbò bò ó ní gbogbo ọjọ́,
Á máa gbé láàárín èjìká rẹ̀.”
13 Ó sọ nípa Jósẹ́fù pé:+
“Kí Jèhófà bù kún ilẹ̀ rẹ̀+
Pẹ̀lú àwọn ohun tó dáa láti ọ̀run,
Pẹ̀lú ìrì àti omi tó ń sun láti ilẹ̀,+
14 Pẹ̀lú àwọn ohun tó dáa tí oòrùn mú jáde,
Àti ohun tó dáa tó ń mú jáde lóṣooṣù,+
15 Pẹ̀lú àwọn ohun tó dáa jù láti àwọn òkè àtijọ́,*+
Àti àwọn ohun tó dáa láti àwọn òkè tó ti wà tipẹ́,
16 Pẹ̀lú àwọn ohun tó dáa ní ayé àti ohun tó kún inú rẹ̀,+
Kí Ẹni tó ń gbé inú igi ẹlẹ́gùn-ún+ sì tẹ́wọ́ gbà á.
Kí wọ́n wá sí orí Jósẹ́fù,
Sí àtàrí ẹni tí a yà sọ́tọ̀ lára àwọn arákùnrin rẹ̀.+
17 Iyì rẹ̀ dà bíi ti àkọ́bí akọ màlúù,
Ìwo akọ màlúù igbó sì ni àwọn ìwo rẹ̀.
Ó máa fi ti* àwọn èèyàn,
Gbogbo wọn pa pọ̀ títí dé àwọn ìkángun ayé.
Ẹgbẹẹgbàárùn-ún Éfúrémù + ni wọ́n,
Ẹgbẹẹgbẹ̀rún Mánásè sì ni wọ́n.”
18 Ó sọ nípa Sébúlúnì pé:+
“Ìwọ Sébúlúnì, máa yọ̀ bí o ṣe ń jáde lọ,
Àti ìwọ Ísákà, nínú àwọn àgọ́ rẹ.+
19 Wọ́n á pe àwọn èèyàn wá sórí òkè.
Ibẹ̀ ni wọ́n á ti rú àwọn ẹbọ òdodo.
20 Ó sọ nípa Gádì pé:+
“Ìbùkún ni fún ẹni tó ń mú kí àwọn ààlà Gádì+ fẹ̀ sí i.
Ó dùbúlẹ̀ síbẹ̀ bíi kìnnìún,
Tó múra tán láti fa apá ya, àní àtàrí.
Àwọn olórí àwọn èèyàn náà máa kóra jọ.
Ó máa mú òdodo Jèhófà ṣẹ
Àti àwọn ìdájọ́ rẹ̀ pẹ̀lú Ísírẹ́lì.”
22 Ó sọ nípa Dánì pé:+
“Ọmọ kìnnìún ni Dánì.+
Ó máa bẹ́ jáde láti Báṣánì.”+
23 Ó sọ nípa Náfútálì pé:+
“Jèhófà ti tẹ́wọ́ gba Náfútálì
Ó sì ti bù kún un lọ́pọ̀lọpọ̀.
Gba ìwọ̀ oòrùn àti gúúsù.”
24 Ó sọ nípa Áṣérì pé:+
“A fi àwọn ọmọ bù kún Áṣérì.
Kó rí ojúure àwọn arákùnrin rẹ̀,
Kó sì ki ẹsẹ̀ rẹ̀ bọ inú òróró.*
25 Irin àti bàbà ni wọ́n fi ṣe ohun tí wọ́n fi ń ti ẹnubodè rẹ,+
O sì máa wà láìséwu ní gbogbo ọjọ́ rẹ.*
Ó máa lé ọ̀tá kúrò níwájú rẹ,+
Ó sì máa sọ pé, ‘Pa wọ́n run!’+
28 Ísírẹ́lì á máa gbé láìséwu,
Orísun Jékọ́bù sì máa wà lọ́tọ̀,
Ní ilẹ̀ tí ọkà àti wáìnì tuntun+ wà,
Tí ìrì á máa sẹ̀ lójú ọ̀run rẹ̀.+
29 Aláyọ̀ ni ọ́, ìwọ Ísírẹ́lì!+
34 Mósè wá kúrò ní aṣálẹ̀ tó tẹ́jú ní Móábù lọ sí Òkè Nébò,+ sí orí Písígà,+ tó dojú kọ Jẹ́ríkò.+ Jèhófà sì fi gbogbo ilẹ̀ náà hàn án, láti Gílíádì títí dé Dánì+ 2 àti gbogbo Náfútálì àti ilẹ̀ Éfúrémù àti Mánásè àti gbogbo ilẹ̀ Júdà títí lọ dé òkun ìwọ̀ oòrùn*+ 3 àti Négébù+ àti Agbègbè,+ pẹ̀tẹ́lẹ̀ Jẹ́ríkò, ìlú tí àwọn igi ọ̀pẹ wà, títí lọ dé Sóárì.+
4 Jèhófà sọ fún un pé: “Ilẹ̀ tí mo búra nípa rẹ̀ fún Ábúráhámù, Ísákì àti Jékọ́bù nìyí pé, ‘Ọmọ* rẹ ni èmi yóò fún.’+ Mo ti jẹ́ kí o fi ojú ara rẹ rí i, àmọ́ o ò ní sọdá sí ibẹ̀.”+
5 Lẹ́yìn náà, Mósè ìránṣẹ́ Jèhófà kú síbẹ̀ ní ilẹ̀ Móábù bí Jèhófà ṣe sọ gẹ́lẹ́.+ 6 Ó sin ín sí àfonífojì ní ilẹ̀ Móábù ní òdìkejì Bẹti-péórì, kò sì sí ẹni tó mọ sàréè rẹ̀ títí di òní yìí.+ 7 Ẹni ọgọ́fà (120) ọdún ni Mósè nígbà tó kú.+ Ojú rẹ̀ ò di bàìbàì, agbára rẹ̀ ò sì dín kù. 8 Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì fi ọgbọ̀n (30) ọjọ́+ sunkún torí Mósè ní aṣálẹ̀ tó tẹ́jú ní Móábù. Nígbà tó yá, ọjọ́ tí wọ́n fi ń sunkún, tí wọ́n sì fi ń ṣọ̀fọ̀ torí Mósè dópin.
9 Ẹ̀mí ọgbọ́n sì kún inú Jóṣúà ọmọ Núnì torí Mósè ti gbé ọwọ́ lé e;+ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì wá ń fetí sí i, wọ́n sì ṣe ohun tí Jèhófà pa láṣẹ fún Mósè gẹ́lẹ́.+ 10 Àmọ́ látìgbà náà, kò tíì sí wòlíì kankan ní Ísírẹ́lì bíi Mósè,+ ẹni tí Jèhófà mọ̀ lójúkojú.+ 11 Ó ṣe gbogbo iṣẹ́ àmì àti iṣẹ́ ìyanu tí Jèhófà ní kó lọ ṣe ní ilẹ̀ Íjíbítì sí Fáráò àti gbogbo àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ àti gbogbo ilẹ̀ rẹ̀,+ 12 pẹ̀lú ọwọ́ agbára àti agbára tó kàmàmà tí Mósè fi hàn lójú gbogbo Ísírẹ́lì.+
Ní Héb., “àwọn ọmọkùnrin Ísírẹ́lì.”
Ó ṣe kedere pé, agbègbè olókè Lẹ́bánónì ló ń sọ.
Ní Héb., “èso.”
Ní Héb., “mú kí ọkàn wa pami.”
Ìyẹn ni pé odi rẹ̀ rí gàgàrà.
Tàbí “àwọsánmà.”
Ní Héb., “tọ Jèhófà lẹ́yìn délẹ̀délẹ̀.”
Tàbí kó jẹ́, “Ọlọ́run ti fún un lágbára.”
Lédè Hébérù, ó tún túmọ̀ sí “ìgbójú” tàbí “ìkọjá àyè.”
Tàbí “Ẹ má ṣe múnú bí wọn.”
Ìyẹn, Kírétè.
Tàbí “wọ́n á ní ìrora bíi ti ẹni tó ń rọbí.”
Tàbí “òkè tí orí rẹ̀ rí pẹrẹsẹ.”
Tàbí kó jẹ́, “Òkúta dúdú.”
Tàbí “pósí.”
Ìgbọ̀nwọ́ kan jẹ́ sẹ̀ǹtímítà 44.5 (ínǹṣì 17.5). Wo Àfikún B14.
Ó túmọ̀ sí “Àwọn Abúlé Jáírì Tí Wọ́n Pàgọ́ Sí.”
Ìyẹn, Òkun Òkú.
Tàbí “kí o sì máa ṣọ́ ọkàn rẹ dáadáa.”
Ní Héb., “títí dé àárín àwọn ọ̀run.”
Tàbí “àwọsánmà.”
Ní Héb., “Ọ̀rọ̀ Mẹ́wàá.”
Tàbí “ẹ ṣọ́ ọkàn yín gidigidi.”
Tàbí “ogún rẹ̀.”
Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀, “Ọkàn.”
Tàbí “ìgbẹ́jọ́.”
Ní Héb., “èso.”
Tàbí “òkè tí orí rẹ̀ rí pẹrẹsẹ.”
Ìyẹn, Òkun Iyọ̀ tàbí Òkun Òkú.
Tàbí “láti fojú di mí.” Ní Héb., “níṣojú mi.”
Tàbí “àwòrán.”
Tàbí “inú rere onífẹ̀ẹ́.”
Ní Héb., “ẹnubodè.”
Ní Héb., “ọ̀rọ̀.”
Tàbí “àwọsánmà.”
Ní Héb., “gbogbo ẹran ara.”
Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀, “Ọkàn.”
Tàbí “okunra rẹ; ohun tí o ní.”
Tàbí “tẹnu mọ́ ọn fún àwọn ọmọ rẹ; tẹ̀ ẹ́ mọ́ àwọn ọmọ rẹ lọ́kàn.”
Ní Héb., “láàárín ojú rẹ.”
Ní Héb., “là ń pa mọ́ níwájú.”
Tàbí “Ẹ ò gbọ́dọ̀ fẹ́ ara yín.”
Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.
Tàbí “tó ṣeyebíye.”
Tàbí “lábẹ́ agbára.”
Ní Héb., “ó máa bù kún èso ikùn rẹ.”
Ní Héb., “Ojú rẹ.”
Tàbí “ìgbẹ́jọ́.”
Tàbí kó jẹ́, “bẹ̀rù; wárìrì.”
Tàbí “ilẹ̀ olómi.”
Tàbí “tó sì ní ibú omi.”
Tàbí “wíìtì.”
Ìyẹn ni pé, odi rẹ̀ rí gàgàrà.
Tàbí “lé wọn kúrò.”
Ní Héb., “ọlọ́rùn líle.”
Tàbí “kóra jọ.”
Tàbí “ère dídà.”
Ní Héb., “ọlọ́rùn líle.”
Tàbí “dídà.”
Tàbí “Ogún.”
Tàbí “ogún.”
Tàbí “áàkì.”
Ní Héb., “Ọ̀rọ̀ Mẹ́wàá.”
Tàbí “kóra jọ.”
Tàbí “ilẹ̀ olómi.”
Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀, “Ọkàn.”
Tàbí “àwọn ọ̀run tó ga jù.”
Ní Héb., “dá ọkàn yín bí ẹni dá adọ̀dọ́.”
Ní Héb., “ẹ má sì mú ọrùn yín le.”
Tàbí “aláìlóbìí.”
Tàbí “ọkàn.”
Tàbí “títí di òní olónìí.”
Tàbí “sí.”
Ní Héb., “èso.”
Tàbí “fi ẹsẹ̀ yín bu omi sí i,” ìyẹn ni pé kí wọ́n fi ẹsẹ̀ wa ẹ̀rọ, ó lè jẹ́ àgbá kẹ̀kẹ́ tó ń bu omi tàbí kí wọ́n fi ẹsẹ̀ la ibi tí omi á máa gbà.
Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀, “Ọkàn.”
Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀, “Ọkàn.”
Ní Héb., “láàárín ojú yín.”
Ìyẹn, Òkun Ńlá, Òkun Mẹditaréníà.
Tàbí “kéde ìbùkún.”
Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.
Tàbí “ohun tó rò pé ó tọ́.”
Ní Héb., “ẹnubodè.”
Tàbí “gbogbo ìgbà tó bá wu ọkàn yín.”
Ní Héb., “nínú gbogbo ẹnubodè.”
Ní Héb., “ẹnubodè.”
Ní Héb., “ẹnubodè.”
Tàbí “ó wu ọkàn rẹ pé kó jẹ ẹran.”
Tàbí “ní gbogbo ìgbà tó bá wu ọkàn rẹ.”
Ní Héb., “ẹnubodè.”
Tàbí “ní gbogbo ìgbà tó bá wu ọkàn rẹ.”
Tàbí “ọkàn.”
Tàbí “ọkàn.”
Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀, “Ọkàn.”
Tàbí “ọ̀rẹ́ rẹ tó jẹ́ ẹni bí ọkàn rẹ.”
Tàbí “tí a ti fòfin dè pé ó jẹ́ ọlọ́wọ̀.”
Tàbí “fetí sí ohùn rẹ̀.”
Ní Héb., “mú kí àárín ojú yín pá.”
Tàbí “tó ṣeyebíye.”
Tàbí “ewúrẹ́ igbó.”
Tàbí “Gbogbo kòkòrò.”
Ní Héb., “ẹnubodè.”
Tàbí “tí ọkàn rẹ bá fẹ́.”
Tàbí “ohunkóhun tí ọkàn rẹ bá ń wá.”
Tàbí “aláìlóbìí.”
Tàbí “gba ohun ìdógò lọ́wọ́ ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè.”
Tàbí “gba ohun ìdógò fún.”
Ní Héb., “ọkàn rẹ.”
Ìyẹn, ohun tí wọ́n fi ń dá nǹkan lu.
Ní Héb., “akọ màlúù.”
Ní Héb., “ẹnubodè.”
Wo Àfikún B15.
Ní Héb., “ẹnubodè.”
Tàbí “aláìlóbìí.”
Ní Héb., “nínú gbogbo ẹnubodè rẹ.”
Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.
Ní Héb., “fi ẹnu sí i.”
Lédè Hébérù, ó tún túmọ̀ sí “ìgbójú” tàbí “ìkọjá àyè.”
Tàbí “àkájọ ìwé.”
Tàbí “wù ú lọ́kàn.”
Ìyẹn, ibi tí Jèhófà yàn pé kí wọ́n ti máa wá jọ́sìn òun.
Tàbí “kóra jọ.”
Lédè Hébérù, ó tún túmọ̀ sí “ìgbójú” tàbí “orí kunkun.”
Ní Héb., “ọkàn tó gbóná.”
Tàbí “ṣe ọkàn rẹ̀ léṣe.”
Ní Héb., “Ojú rẹ.”
Ní Héb., “dìde lòdì sí ẹnì kan torí.”
Ní Héb., “Láti ẹnu.”
Ní Héb., “Ojú rẹ.”
Tàbí “ọkàn.”
Tàbí “ọkàn.”
Tàbí “kó ìpayà bá àwọn arákùnrin rẹ̀ bíi tirẹ̀.”
Tàbí “tí ọkàn rẹ̀ bá fẹ́.”
Ní Héb., “ìyàwó méjì, ó nífẹ̀ẹ́ ọ̀kan, ó sì kórìíra ìkejì.”
Tàbí “ta á nù.”
Tàbí “ta á nù.”
Ṣékélì kan jẹ́ gíráàmù 11.4. Wo Àfikún B14.
Tàbí “aṣẹ́wó.”
Tàbí “pa ọkàn náà.”
Ní Héb., “ṣí aṣọ lára bàbá rẹ̀.”
Tàbí “pe ibi wá sórí.”
Tàbí “tó ń sọni di aláìmọ́.”
Ìyẹn, ilé ìyàgbẹ́.
Tàbí “owó tí ọkùnrin kan gbà.”
Ní Héb., “owó tí wọ́n san fún ajá.”
Tàbí “ọkàn rẹ.”
Tàbí “kọ̀ ọ́.”
Tàbí “ìdógò.”
Tàbí “torí ẹ̀mí onítọ̀hún; torí ọkàn onítọ̀hún.”
Tàbí “ọkàn kan.”
Ọ̀rọ̀ Hébérù tí wọ́n tú sí “ẹ̀tẹ̀” ní ìtumọ̀ tó pọ̀, ó lè túmọ̀ sí oríṣiríṣi àrùn tó máa ń wà ní awọ ara, tó sì lè ran ẹlòmíì. Ó tún lè jẹ́ àwọn àrùn kan tó máa ń wà lára aṣọ tàbí lára ilé.
Ní Héb., “ẹnubodè.”
Tàbí “ọkàn.”
Tàbí “aláìlóbìí.”
Tàbí “ìdógò.”
Tàbí “orúkọ agbo ilé rẹ̀.” Ní Héb., “orúkọ rẹ̀.”
Ní Héb., “Ojú rẹ.”
Ní Héb., “eéfà àti eéfà nínú ilé rẹ.” Wo Àfikún B14.
Ní Héb., “èso.”
Tàbí kó jẹ́, “tó ń kú lọ.”
Tàbí “aláìlóbìí.”
Ní Héb., “ẹnubodè.”
Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀, “Ọkàn.”
Tàbí “tó ṣeyebíye.”
Tàbí “kùn ún lẹ́fun.”
Tàbí “kùn ún lẹ́fun.”
Tàbí “ère dídà.”
Tàbí “oníṣẹ́ igi àti irin.”
Tàbí “Bẹ́ẹ̀ ni kó rí.”
Tàbí “aláìlóbìí.”
Ní Héb., “ṣí aṣọ lára bàbá rẹ̀.”
Tàbí “láti ṣá ẹni tí kò mọwọ́ mẹsẹ̀ balẹ̀.”
Ní Héb., “èso ikùn.”
Ní Héb., “èso ikùn.”
Tàbí “kí ọkàn rẹ sì dà rú.”
Ní Héb., “àfipòwe.”
Tàbí “Àwọn kòkòrò tó ń kùn yùnmù.”
Ní Héb., “ẹnubodè.”
Ní Héb., “èso ikùn.”
Tàbí “ìrẹ̀wẹ̀sì ọkàn.”
Tàbí “ìgbẹ́jọ́.”
Ó ṣeé ṣe kí ọ̀rọ̀ Hébérù yìí ní í ṣe pẹ̀lú ọ̀rọ̀ tí wọ́n ń lò fún “ìgbẹ́,” wọ́n sì máa ń lò ó fún ohun tí wọ́n bá kórìíra.
Ìyẹn, igi kan tó korò gan-an.
Ní Héb., “ohun tí a bomi rin dáadáa pẹ̀lú ohun tó gbẹ.”
Ní Héb., “tí kò sì yàn fún wọn.”
Ní Héb., “mú wọn pa dà wá sínú ọkàn rẹ.”
Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀, “Ọkàn.”
Ní Héb., “dádọ̀dọ́ ọkàn rẹ.”
Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀, “Ọkàn.”
Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀, “Ọkàn.”
Ní Héb., “kò sì jìnnà sí ọ.”
Ní Héb., “Mi ò lè máa jáde kí n sì máa wọlé mọ́.”
Ní Héb., “àwọn ọmọ kéékèèké.”
Ní Héb., “ẹnubodè.”
Tàbí “lọ dúró níwájú.”
Tàbí “àwọsánmà tó rí bí òpó.”
Ní Héb., “dùbúlẹ̀ pẹ̀lú àwọn bàbá rẹ.”
Ní Héb., “Ẹ fi sí wọn lẹ́nu.”
Ní Héb., “tí wọ́n sì sanra.”
Ó ṣe kedere pé Ọlọ́run ló ń tọ́ka sí.
Ní Héb., “ẹ sì jẹ́ ọlọ́rùn líle.”
Tàbí kó jẹ́, “ìran èèyàn.”
Ìyẹn, Jékọ́bù.
Ní Héb., “ọ̀rá àgùntàn.”
Tàbí “wíìtì.”
Ní Héb., “ọ̀rá kíndìnrín àlìkámà.”
Tàbí “omi.”
Ó túmọ̀ sí “Adúróṣinṣin,” orúkọ oyè tí wọ́n fún Ísírẹ́lì.
Tàbí “mú kí n jowú.”
Tàbí “Ṣìọ́ọ̀lù,” ìyẹn ibojì aráyé. Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.
Tàbí kó jẹ́, “tó kọ etí ikún sí ìmọ̀ràn.”
Tàbí “pèrò dà nípa.”
Tàbí “ẹbọ wọn tó dáa jù.”
Tàbí “wẹ ilẹ̀ àwọn èèyàn rẹ̀ mọ́.”
Orúkọ tí Jóṣúà ń jẹ́ gangan. Hóṣéà ni ìkékúrú Hòṣáyà, ó túmọ̀ sí “Ẹni Tí Jáà Gbà Là; Jáà Ti Gbà Là.”
Àkànlò èdè yìí ni wọ́n fi ń sọ pé èèyàn kú.
Tàbí “ẹgbẹẹgbàárùn-ún.”
Ó túmọ̀ sí “Adúróṣinṣin,” orúkọ oyè tí wọ́n fún Ísírẹ́lì.
Tàbí “jà fún.”
Nínú ẹsẹ yìí, “rẹ” àti “ọ” ń tọ́ka sí Ọlọ́run.
Ní Héb., “sínú imú rẹ.”
Tàbí “ìbàdí.”
Tàbí kó jẹ́, “àwọn òkè ìlà oòrùn.”
Tàbí “kan.”
Ní Héb., “fa ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ ohun tó wà nínú.”
Tàbí “ìṣúra.”
Tàbí “wẹ ẹsẹ̀ rẹ̀ nínú òróró.”
Ní Héb., “Agbára rẹ yóò sì rí bí àwọn ọjọ́ rẹ.”
Tàbí “ìkùukùu.”
Tàbí kó jẹ́, “àwọn ibi gíga.”
Ìyẹn, Òkun Ńlá, Òkun Mẹditaréníà.
Ní Héb., “Èso.”