ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • nwt Aísáyà 1:1-66:24
  • Àìsáyà

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àìsáyà
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
Àìsáyà

ÀÌSÁYÀ

1 Ìran tí Àìsáyà*+ ọmọ Émọ́ọ̀sì rí nípa Júdà àti Jerúsálẹ́mù láyé ìgbà Ùsáyà,+ Jótámù,+ Áhásì+ àti Hẹsikáyà,+ àwọn ọba Júdà:+

 2 Ẹ gbọ́, ẹ̀yin ọ̀run, sì fetí sílẹ̀, ìwọ ayé,+

Torí Jèhófà ti sọ pé:

“Mo ti tọ́ àwọn ọmọ,+ mo sì ti tọ́jú wọn dàgbà,

Àmọ́ wọ́n ti ṣọ̀tẹ̀ sí mi.+

 3 Akọ màlúù mọ ẹni tó ra òun dunjú,

Kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ sì mọ ibùjẹ ẹran olówó rẹ̀;

Àmọ́ Ísírẹ́lì ò mọ̀ mí,*+

Àwọn èèyàn mi ò fi òye hùwà.”

 4 O gbé! Ìwọ orílẹ̀-èdè ẹlẹ́ṣẹ̀,+

Àwọn èèyàn tí ẹ̀ṣẹ̀ wọ̀ lọ́rùn,

Ìran àwọn èèyàn burúkú, àwọn ọmọ oníwà ìbàjẹ́!

Wọ́n ti fi Jèhófà sílẹ̀;+

Wọ́n ti hùwà àfojúdi sí Ẹni Mímọ́ Ísírẹ́lì;

Wọ́n ti kẹ̀yìn sí i.

 5 Ibo la tún lè lù lára yín nígbà tí ẹ kò jáwọ́ nínú ìwà ọ̀tẹ̀ yín?+

Gbogbo orí yín ló ń ṣàìsàn

Àrùn sì ti kọ lu gbogbo ọkàn yín.+

 6 Láti àtẹ́lẹsẹ̀ dé orí, kò sí ibi tó gbádùn.

Ara yín bó, ó ní ọgbẹ́ àti ojú egbò,

Ẹ ò tọ́jú wọn,* ẹ ò dì wọ́n, ẹ ò sì fi òróró pa wọ́n.+

 7 Ilẹ̀ yín ti di ahoro.

Wọ́n ti dáná sun àwọn ìlú yín.

Àwọn àjèjì jẹ ilẹ̀ yín run níṣojú yín.+

Ó dà bí ilẹ̀ tó di ahoro tí àwọn àjèjì gbà.+

 8 Ó wá ku ọmọbìnrin Síónì nìkan, bí àtíbàbà nínú ọgbà àjàrà,

Bí ahéré nínú oko kùkúńbà,*

Bí ìlú tí wọ́n gbógun tì.+

 9 Tí kì í bá ṣe pé Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun dá díẹ̀ nínú wa sí,

À bá ti dà bíi Sódómù gẹ́lẹ́,

À bá sì ti jọ Gòmórà.+

10 Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ Jèhófà, ẹ̀yin apàṣẹwàá* Sódómù.+

Ẹ fetí sí òfin* Ọlọ́run wa, ẹ̀yin èèyàn Gòmórà.+

11 “Àǹfààní wo ni ọ̀pọ̀ ẹbọ yín ń ṣe mí?”+ ni Jèhófà wí.

“Àwọn ẹbọ sísun yín tí ẹ fi àgbò+ ṣe àti ọ̀rá àwọn ẹran tí ẹ bọ́ dáadáa + ti sú mi,

Inú mi ò dùn sí ẹ̀jẹ̀+ àwọn akọ ọmọ màlúù,+ ọ̀dọ́ àgùntàn àti ewúrẹ́.+

12 Bí ẹ ṣe ń wá síwájú mi,+

Tí ẹ̀ ń tẹ àgbàlá mi mọ́lẹ̀,

Ta ló ní kí ẹ ṣe bẹ́ẹ̀?+

13 Ẹ má ṣe mú àwọn ọrẹ ọkà tí kò ní láárí wá mọ́.

Tùràrí yín ń rí mi lára.+

Àwọn òṣùpá tuntun,+ sábáàtì+ àti pípe àpéjọ,+

Mi ò lè fara da bí ẹ ṣe ń pidán,+ tí ẹ sì tún ń ṣe àpéjọ ọlọ́wọ̀.

14 Mo* kórìíra àwọn òṣùpá tuntun yín àtàwọn àjọyọ̀ yín.

Wọ́n ti di ẹrù ìnira fún mi;

Mi ò lè gbé e mọ́.

15 Tí ẹ bá sì tẹ́ ọwọ́ yín,

Mò ń fojú mi pa mọ́ fún yín.+

Bí ẹ tiẹ̀ ń gbàdúrà púpọ̀,+

Mi ò gbọ́ àdúrà yín;+

Ẹ̀jẹ̀ kún ọwọ́ yín.+

16 Ẹ wẹ ara yín, ẹ jẹ́ kí ara yín mọ́;+

Ẹ mú ìwà ibi yín kúrò níwájú mi;

Ẹ jáwọ́ nínú ìwà burúkú.+

17 Ẹ kọ́ bí ẹ ṣe máa ṣe rere, ẹ wá ìdájọ́ òdodo,+

Ẹ tọ́ àwọn aninilára sọ́nà;

Ẹ gbèjà àwọn ọmọ aláìníbaba,*

Kí ẹ sì gba ẹjọ́ opó rò.”+

18 “Ní báyìí, ẹ wá, ẹ jẹ́ ká yanjú ọ̀rọ̀ láàárín ara wa,” ni Jèhófà wí.+

“Bí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ yín tiẹ̀ rí bí aṣọ rírẹ̀dòdò,

Wọ́n máa di funfun bíi yìnyín;+

Bí wọ́n tiẹ̀ pọ́n bí aṣọ tó pupa yòò,

Wọ́n máa dà bí irun àgùntàn.

19 Tó bá tinú yín wá, tí ẹ sì fetí sílẹ̀,

Ẹ máa jẹ àwọn ohun rere ilẹ̀ náà.+

20 Àmọ́ tí ẹ bá kọ̀, tí ẹ sì ṣọ̀tẹ̀,

Idà máa jẹ yín run,+

Torí Jèhófà ti fi ẹnu rẹ̀ sọ ọ́.”

21 Ẹ wo bí ìlú olóòótọ́+ ṣe di aṣẹ́wó!+

Ìdájọ́ òdodo kún inú rẹ̀ tẹ́lẹ̀;+

Òdodo ń gbé inú rẹ̀ nígbà kan,+

Àmọ́ ní báyìí, àwọn apààyàn ló wà níbẹ̀.+

22 Fàdákà rẹ ti di ìdàrọ́,+

Wọ́n sì ti bu omi la ọtí bíà rẹ.*

23 Alágídí ni àwọn ìjòyè rẹ, àwọn àtàwọn olè jọ ń ṣiṣẹ́.+

Gbogbo wọn ló fẹ́ràn àbẹ̀tẹ́lẹ̀, wọ́n sì ń wá ẹ̀bùn kiri.+

Wọn kì í dá ẹjọ́ àwọn ọmọ aláìníbaba* bó ṣe tọ́,

Ẹjọ́ opó kì í sì í dé iwájú wọn.+

24 Torí náà, Olúwa tòótọ́, Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun,

Alágbára Ísírẹ́lì, kéde pé:

“Ó tó gẹ́ẹ́! Mi ò ní fàyè gba àwọn elénìní mi mọ́,

Màá sì gbẹ̀san lára àwọn ọ̀tá mi.+

25 Màá yí ọwọ́ mi pa dà sí ọ,

Màá yọ́ ìdàrọ́ rẹ dà nù bíi pé mo fi ọṣẹ fọ ìdọ̀tí,

Màá sì mú gbogbo ìdọ̀tí rẹ kúrò.+

26 Màá dá àwọn adájọ́ rẹ pa dà sí bí wọ́n ṣe wà níbẹ̀rẹ̀,

Àwọn agbani-nímọ̀ràn rẹ á sì rí bíi ti ìbẹ̀rẹ̀.+

Lẹ́yìn èyí, wọ́n máa pè ọ́ ní Ìlú Òdodo, Ìlú Olóòótọ́.+

27 Ìdájọ́ òdodo la máa fi tún Síónì rà pa dà,+

Àwọn èèyàn rẹ̀ tó pa dà la sì máa fi òdodo rà pa dà.

28 Àwọn ọlọ̀tẹ̀ àti àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ jọ máa fọ́ sí wẹ́wẹ́,+

Òpin sì máa dé bá àwọn tó ń fi Jèhófà sílẹ̀.+

29 Torí àwọn igi ńlá tó wù yín máa tì wọ́n lójú,+

Ojú sì máa tì yín torí àwọn ọgbà* tí ẹ yàn.+

30 Torí ẹ máa dà bí igi ńlá tí àwọn ewé rẹ̀ rọ+

Àti bí ọgbà tí kò lómi.

31 Ọkùnrin alágbára máa di èétú okùn,*

Iṣẹ́ rẹ̀ sì máa ta pàrà;

Iná máa jó àwọn méjèèjì pa pọ̀,

Kò sì ní sẹ́ni tó máa pa iná náà.”

2 Ohun tí Àìsáyà ọmọ Émọ́ọ̀sì rí nípa Júdà àti Jerúsálẹ́mù nìyí:+

 2 Ní apá ìgbẹ̀yìn àwọn ọjọ́,*

Òkè ilé Jèhófà

Máa fìdí múlẹ̀ gbọn-in sórí àwọn òkè,+

A sì máa gbé e ga ju àwọn òkè kéékèèké lọ,

Gbogbo orílẹ̀-èdè á sì máa rọ́ lọ síbẹ̀.+

 3 Ọ̀pọ̀ èèyàn máa lọ, wọ́n á sì sọ pé:

“Ẹ wá, ẹ jẹ́ ká lọ sórí òkè Jèhófà,

Sí ilé Ọlọ́run Jékọ́bù.+

Ó máa kọ́ wa ní àwọn ọ̀nà rẹ̀,

A ó sì máa rìn ní àwọn ọ̀nà rẹ̀.”+

Torí òfin* máa jáde láti Síónì,

Ọ̀rọ̀ Jèhófà sì máa jáde láti Jerúsálẹ́mù.+

 4 Ó máa ṣe ìdájọ́ láàárín àwọn orílẹ̀-èdè,

Ó sì máa yanjú ọ̀rọ̀* láàárín ọ̀pọ̀ èèyàn.

Wọ́n máa fi idà wọn rọ ohun ìtúlẹ̀,

Wọ́n sì máa fi ọ̀kọ̀ wọn rọ ohun ìrẹ́wọ́ ọ̀gbìn.+

Àwọn orílẹ̀-èdè kò ní yọ idà sí ara wọn mọ́,

Wọn ò sì ní kọ́ṣẹ́ ogun mọ́.+

 5 Ẹ̀yin ilé Jékọ́bù, ẹ wá,

Ẹ jẹ́ ká rìn nínú ìmọ́lẹ̀ Jèhófà.+

 6 Torí o ti pa àwọn èèyàn rẹ, ilé Jékọ́bù tì.+

Torí àwọn nǹkan tó wá láti Ìlà Oòrùn ti kún ọwọ́ wọn;

Wọ́n ń pidán+ bí àwọn Filísínì,

Àwọn ọmọ àjèjì sì pọ̀ láàárín wọn.

 7 Fàdákà àti wúrà kún ilẹ̀ wọn,

Ìṣúra wọn kò sì lópin.

Ẹṣin kún ilẹ̀ wọn,

Kẹ̀kẹ́ ẹṣin wọn ò sì níye.+

 8 Àwọn ọlọ́run tí kò ní láárí kún ilẹ̀ wọn.+

Wọ́n ń forí balẹ̀ fún iṣẹ́ ọwọ́ ara wọn,

Fún ohun tí wọ́n fi ìka ara wọn ṣe.

 9 Èèyàn wá ń forí balẹ̀, ó di ẹni tó rẹlẹ̀,

O ò sì lè dárí jì wọ́n.

10 Wọ inú àpáta, kí o sì fi ara rẹ pa mọ́ sínú iyẹ̀pẹ̀,

Torí bí Jèhófà ṣe wà níbí ń dẹ́rù bani,

Iyì rẹ̀ sì ga lọ́lá.+

11 Ojú èèyàn tó ń gbéra ga máa wálẹ̀,

A sì máa tẹrí ìgbéraga àwọn èèyàn ba.*

Jèhófà nìkan la máa gbé ga ní ọjọ́ yẹn.

12 Torí ọjọ́ Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun ni.+

Ó ń bọ̀ wá sórí gbogbo ẹni tó ń gbéra ga àti ẹni gíga,

Sórí gbogbo èèyàn, ì báà jẹ́ ẹni gíga tàbí ẹni tó rẹlẹ̀,+

13 Sórí gbogbo igi kédárì Lẹ́bánónì tó ga, tó sì ta yọ

Àti sórí gbogbo igi ràgàjì* Báṣánì,

14 Sórí gbogbo òkè ńláńlá

Àti sórí gbogbo òkè tó ga,

15 Sórí gbogbo ilé gogoro àti gbogbo odi ààbò,

16 Sórí gbogbo ọkọ̀ òkun Táṣíṣì+

Àti sórí gbogbo ọkọ̀ ojú omi tó wuni.

17 Ìgbéraga èèyàn máa wálẹ̀,

A sì máa tẹrí ìgbéraga àwọn èèyàn ba.*

Jèhófà nìkan la máa gbé ga ní ọjọ́ yẹn.

18 Àwọn ọlọ́run tí kò ní láárí máa pòórá pátápátá.+

19 Àwọn èèyàn sì máa wọ ihò inú àpáta

Àti àwọn ihò inú ilẹ̀,+

Torí bí Jèhófà ṣe wà níbí ń dẹ́rù bani,

Iyì rẹ̀ sì ga lọ́lá,+

Nígbà tó dìde láti mi ayé jìgìjìgì, kó sì kó jìnnìjìnnì bá a.

20 Ní ọjọ́ yẹn, àwọn èèyàn máa mú àwọn ọlọ́run wọn tí kò ní láárí, tí wọ́n fi fàdákà àti wúrà ṣe,

Èyí tí wọ́n ṣe fúnra wọn kí wọ́n lè máa forí balẹ̀ fún un,

Wọ́n á sì jù wọ́n sí àwọn asín* àti àwọn àdán,+

21 Kí wọ́n lè wọ àwọn ihò inú àpáta

Àti inú àwọn pàlàpálá àpáta,

Torí bí Jèhófà ṣe wà níbí ń dẹ́rù bani,

Iyì rẹ̀ sì ga lọ́lá,

Nígbà tó dìde láti mi ayé jìgìjìgì, kó sì kó jìnnìjìnnì bá a.

22 Fún àǹfààní ara yín, ẹ má ṣe gbẹ́kẹ̀ lé èèyàn lásán mọ́,

Ẹni tí kò yàtọ̀ sí èémí ihò imú rẹ̀.*

Kí nìdí tí ẹ fi máa kà á sí?

3 Wò ó! Olúwa tòótọ́, Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun,

Ó ń mú gbogbo ìtìlẹ́yìn àtàwọn ohun tí wọ́n nílò ní Jerúsálẹ́mù àti Júdà kúrò,

Gbogbo ìtìlẹ́yìn oúnjẹ àti omi,+

 2 Akíkanjú ọkùnrin àti jagunjagun,

Adájọ́ àti wòlíì,+ woṣẹ́woṣẹ́ àtàwọn àgbààgbà,

 3 Olórí àádọ́ta (50),+ èèyàn pàtàkì àti agbani-nímọ̀ràn,

Onídán tó gbówọ́ àti atujú tó gbóná.+

 4 Àwọn ọmọdékùnrin ni màá fi ṣe olórí wọn,

Àwọn aláìnípinnu* ló sì máa ṣàkóso wọn.

 5 Àwọn èèyàn náà máa fìyà jẹ ara wọn,

Kálukú máa fìyà jẹ ọmọnìkejì rẹ̀.+

Ọmọdékùnrin máa lu àgbà ọkùnrin,

Ẹni tí wọn ò fi bẹ́ẹ̀ kà sí sì máa fojú di ẹni táwọn èèyàn bọ̀wọ̀ fún.+

 6 Kálukú máa mú arákùnrin rẹ̀ nínú ilé bàbá rẹ̀, á sì sọ pé:

“O ní aṣọ àwọ̀lékè, wá ṣe olórí wa.

Jẹ́ kí àwókù ibi tí a ṣẹ́gun yìí wà níkàáwọ́ rẹ.”

 7 Àmọ́ ó máa kọ̀ jálẹ̀ ní ọjọ́ yẹn pé:

“Mi ò ní wẹ ọgbẹ́ rẹ;*

Mi ò ní oúnjẹ tàbí aṣọ nínú ilé mi.

Ẹ má fi mí ṣe olórí àwọn èèyàn náà.”

 8 Torí Jerúsálẹ́mù ti kọsẹ̀,

Júdà sì ti ṣubú,

Torí wọ́n ta ko Jèhófà nínú ọ̀rọ̀ àti ìṣe wọn;

Wọ́n ya aláìgbọràn níwájú ògo rẹ̀.*+

 9 Ìrísí ojú wọn ta kò wọ́n,

Wọ́n sì ń kéde ẹ̀ṣẹ̀ wọn bíi ti Sódómù;+

Wọn ò fi bò rárá.

Wọ́n* gbé, torí wọ́n ń mú àjálù wá sórí ara wọn!

10 Sọ fún àwọn olódodo pé nǹkan máa lọ dáadáa fún wọn;

Wọ́n máa jèrè iṣẹ́ ọwọ́ wọn.*+

11 Ẹni burúkú gbé!

Àjálù máa dé bá a,

Torí ohun tó fi ọwọ́ ara rẹ̀ ṣe ni wọ́n máa ṣe fún un!

12 Ní ti àwọn èèyàn mi, àwọn tó ń kó wọn ṣiṣẹ́ ń fìyà jẹ wọ́n,

Àwọn obìnrin sì ń jọba lé wọn lórí.

Ẹ̀yin èèyàn mi, àwọn olórí yín ń mú kí ẹ rìn gbéregbère,

Wọ́n sì ń da ọ̀nà rú mọ́ yín lójú.+

13 Jèhófà dúró sí àyè rẹ̀ láti fẹ̀sùn kàn wọ́n;

Ó dìde dúró láti ṣèdájọ́ àwọn èèyàn.

14 Jèhófà máa dá àwọn àgbààgbà àtàwọn olórí àwọn èèyàn rẹ̀ lẹ́jọ́.

“Ẹ ti dáná sun ọgbà àjàrà.

Ohun tí ẹ jí lọ́dọ̀ aláìní sì wà nínú àwọn ilé yín.+

15 Kí ló kì yín láyà tí ẹ fi ń tẹ àwọn èèyàn mi rẹ́,

Tí ẹ sì ń fi ojú àwọn aláìní gbolẹ̀?”+ ni Olúwa Ọba Aláṣẹ, Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun wí.

16 Jèhófà sọ pé: “Torí pé àwọn ọmọbìnrin Síónì ń gbéra ga,

Tí wọ́n ń gbé orí wọn sókè* bí wọ́n ṣe ń rìn,

Tí wọ́n ń sejú, tí wọ́n sì ń ṣakọ lọ,

Wọ́n ń mú kí ẹ̀gbà ẹsẹ̀ wọn máa dún woroworo,

17 Jèhófà tún máa fi èépá kọ lu àwọn ọmọbìnrin Síónì ní orí,

Jèhófà sì máa mú kí iwájú orí wọn pá.+

18 Ní ọjọ́ yẹn, Jèhófà ò ní mú kí àwọn ẹ̀gbà ọwọ́ àti ẹsẹ̀ wọn rẹwà mọ́,

Àwọn aṣọ ìwérí àtàwọn ohun ọ̀ṣọ́ tó rí bí òṣùpá,+

19 Àwọn yẹtí,* àwọn ẹ̀gbà ọwọ́ àti ìbòjú,

20 Àwọn ìwérí, àwọn ẹ̀gbà ẹsẹ̀ àtàwọn ọ̀já ìgbàyà,*

Àwọn ìgò lọ́fínńdà* àtàwọn oògùn,*

21 Àwọn òrùka ọwọ́ àti òrùka imú,

22 Àwọn aṣọ oyè, àwọn aṣọ àwọ̀lékè, àwọn aṣọ ìlékè àtàwọn àpò,

23 Àwọn dígí ọwọ́+ àtàwọn aṣọ ọ̀gbọ̀,*

Àwọn láwàní àtàwọn ìbòjú.

24 Dípò òróró básámù,+ òórùn ohun tó jẹrà ló máa wà;

Dípò àmùrè, okùn;

Dípò irun tó rẹwà, orí pípá;+

Dípò aṣọ olówó ńlá, aṣọ ọ̀fọ̀;*+

Àpá tí wọ́n fi sàmì dípò ẹwà.

25 Wọ́n máa fi idà pa àwọn ọkùnrin rẹ,

Àwọn akíkanjú ọkùnrin rẹ sì máa kú sójú ogun.+

26 Àwọn ẹnu ọ̀nà rẹ̀ máa ṣọ̀fọ̀, wọ́n á sì kẹ́dùn,+

Ó sì máa jókòó sí ilẹ̀, ó máa di ahoro.”+

4 Obìnrin méje á di ọkùnrin kan mú ní ọjọ́ yẹn,+ wọ́n á sọ pé:

“Oúnjẹ tiwa ni a ó máa jẹ,

Aṣọ wa ni a ó sì máa wọ̀;

Ṣáà jẹ́ kí wọ́n máa fi orúkọ rẹ pè wá,

Láti mú ìtìjú* wa kúrò.”+

2 Ní ọjọ́ yẹn, ohun tí Jèhófà mú kó rú jáde máa ga lọ́lá, ògo rẹ̀ sì máa yọ, èso ilẹ̀ náà máa jẹ́ ohun àmúyangàn àti ẹwà fún àwọn tó bá yè bọ́ ní Ísírẹ́lì.+ 3 A máa pe ẹnikẹ́ni tó bá ṣẹ́ kù ní Síónì àti Jerúsálẹ́mù ní mímọ́, gbogbo àwọn tó wà ní Jerúsálẹ́mù tí a kọ sílẹ̀ pé kí wọ́n wà láàyè.+

4 Nígbà tí Jèhófà bá fọ ẹ̀gbin* àwọn ọmọbìnrin Síónì kúrò,+ tó sì fi ẹ̀mí ìdájọ́ àti ẹ̀mí tó ń jó* ṣan ìtàjẹ̀sílẹ̀ Jerúsálẹ́mù kúrò láàárín rẹ̀,+ 5 ní ọ̀sán, Jèhófà tún máa mú kí ìkùukùu* àti èéfín wà lórí gbogbo ibi tí Òkè Síónì wà àti lórí ibi tí wọ́n máa ń pé jọ sí níbẹ̀, ó sì máa mú kí iná tó mọ́lẹ̀, tó ń jó lala wà níbẹ̀ ní òru;+ torí pé ààbò máa wà lórí gbogbo ògo náà. 6 Ní ọ̀sán, àtíbàbà kan máa ṣíji bò wọ́n lọ́wọ́ ooru,+ ó máa jẹ́ ibi ààbò, ó sì máa dáàbò bò wọ́n lọ́wọ́ ìjì àti òjò.+

5 Jọ̀ọ́, jẹ́ kí n kọrin fún ẹni tí mo fẹ́ràn,

Orin tó dá lórí ẹni tí mo nífẹ̀ẹ́ àti ọgbà àjàrà rẹ̀.+

Ẹni tí mo fẹ́ràn ní ọgbà àjàrà kan síbi òkè tó lọ́ràá.

 2 Ó gbẹ́ ibẹ̀, ó sì kó àwọn òkúta ibẹ̀ kúrò.

Ó gbin àjàrà pupa tó dáa sínú rẹ̀,

Ó kọ́ ilé gogoro sí àárín rẹ̀,

Ó sì gbẹ́ ibi tí wọ́n ti ń fún wáìnì sínú rẹ̀.+

Ó wá ń retí pé kí àjàrà náà so,

Àmọ́ èso àjàrà igbó nìkan ló mú jáde. +

 3 “Ní báyìí, ẹ̀yin tí ẹ̀ ń gbé Jerúsálẹ́mù àti ẹ̀yin èèyàn Júdà,

Ẹ jọ̀ọ́, ẹ ṣèdájọ́ láàárín èmi àti ọgbà àjàrà mi.+

 4 Kí ló tún yẹ kí n ṣe fún ọgbà àjàrà mi

Tí mi ò tíì ṣe?+

Nígbà tí mo retí pé kó so èso àjàrà,

Kí ló dé tó jẹ́ àjàrà igbó nìkan ló ń mú jáde?

 5 Ó yá, ẹ jọ̀ọ́, ẹ jẹ́ kí n sọ fún yín,

Ohun tí màá ṣe sí ọgbà àjàrà mi:

Màá mú ọgbà tó yí i ká kúrò,

Màá sì dáná sun ún.+

Màá fọ́ ògiri olókùúta rẹ̀,

Wọ́n sì máa tẹ̀ ẹ́ mọ́lẹ̀.

 6 Màá sọ ọ́ di ahoro;+

Wọn ò ní rẹ́wọ́ rẹ̀, wọn ò sì ní ro ó.

Igi ẹlẹ́gùn-ún àti èpò ló máa kún ibẹ̀,+

Màá sì pàṣẹ fún àwọsánmà* pé kó má rọ òjò kankan sórí rẹ̀.+

 7 Torí pé ilé Ísírẹ́lì ni ọgbà àjàrà Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun;+

Àwọn èèyàn Júdà sì ni oko* tó fẹ́ràn.

Ó ń retí ìdájọ́ òdodo,+

Àmọ́ wò ó! ìrẹ́jẹ ló wà;

Ó ń retí òdodo,

Àmọ́ wò ó! igbe ìdààmú ló wà.”+

 8 Àwọn tó ń ní ilé kún ilé gbé +

Àti àwọn tí wọ́n ń ní ilẹ̀ kún ilẹ̀,+

Títí kò fi sí àyè mọ́,

Tó sì wá ku ẹ̀yin nìkan lórí ilẹ̀ náà!

 9 Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun ti búra ní etí mi,

Pé ọ̀pọ̀ ilé, bí wọ́n tiẹ̀ tóbi, tí wọ́n sì rẹwà,

Wọ́n máa di ohun àríbẹ̀rù,

Láìsí olùgbé kankan.+

10 Torí pé òṣùwọ̀n báàtì* kan ṣoṣo ni éékà ilẹ̀ mẹ́wàá* tí wọ́n gbin àjàrà sí máa mú jáde,

Eéfà* kan ṣoṣo sì ni irúgbìn tó jẹ́ òṣùwọ̀n hómérì* kan máa mú jáde.+

11 Àwọn tó ń dìde mu ọtí láàárọ̀ kùtù gbé,+

Tí wọ́n ń dúró síbẹ̀ dìgbà tílẹ̀ ṣú títí ọtí fi ń pa wọ́n!

12 Wọ́n ní háàpù àti ohun ìkọrin olókùn tín-ín-rín,

Ìlù tanboríìnì, fèrè àti wáìnì sì wà níbi àsè wọn;

Àmọ́ wọn ò ronú nípa iṣẹ́ Jèhófà,

Wọn ò sì rí iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀.

13 Torí náà, àwọn èèyàn mi máa lọ sí ìgbèkùn,

Torí wọn ò ní ìmọ̀;+

Ebi máa pa àwọn èèyàn wọn tó lọ́lá,+

Òùngbẹ sì máa gbẹ gbogbo èèyàn wọn gidigidi.

14 Torí náà, Isà Òkú* ti fẹ ara* rẹ̀ sí i,

Ó sì ti la ẹnu rẹ̀ sílẹ̀ gbayawu láìní ààlà;+

Ó dájú pé iyì rẹ̀,* ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ èèyàn rẹ̀ tí wọ́n ń pariwo àtàwọn èèyàn rẹ̀ tó ń ṣe àríyá aláriwo

Máa sọ̀ kalẹ̀ lọ sínú rẹ̀.

15 Èèyàn sì máa tẹrí ba,

A máa rẹ èèyàn sílẹ̀,

A sì máa rẹ ojú àwọn agbéraga wálẹ̀.

16 Ìdájọ́* Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun máa gbé e ga,

Ọlọ́run tòótọ́, Ẹni Mímọ́,+ máa fi òdodo+ sọ ara rẹ̀ di mímọ́.

17 Àwọn ọ̀dọ́ àgùntàn sì máa jẹko bíi pé ibi ìjẹko wọn ni;

Àwọn àjèjì máa jẹun níbi tó ti dahoro táwọn ẹran tí wọ́n bọ́ dáadáa ti jẹun.

18 Àwọn tó ń fi okùn ẹ̀tàn fa ẹ̀bi wọn lọ gbé,

Tí wọ́n sì ń fi okùn kẹ̀kẹ́ ẹṣin fa ẹ̀ṣẹ̀ wọn;

19 Àwọn tó ń sọ pé: “Kó jẹ́ kí iṣẹ́ Rẹ̀ yára kánkán;

Kó tètè dé, ká lè rí i.

Kí ohun tí Ẹni Mímọ́ Ísírẹ́lì ní lọ́kàn* ṣẹ,

Ká lè mọ̀ ọ́n!”+

20 Àwọn tó ń sọ pé ohun tó dára burú àti pé ohun tó burú dára gbé,+

Àwọn tó ń fi òkùnkùn dípò ìmọ́lẹ̀, tí wọ́n sì ń fi ìmọ́lẹ̀ dípò òkùnkùn,

Àwọn tó ń fi ìkorò dípò adùn àti adùn dípò ìkorò!

21 Àwọn tó gbọ́n lójú ara wọn gbé,

Tí wọ́n jẹ́ olóye lójú ara wọn!+

22 Àwọn akọni nídìí ọtí mímu gbé

Àti àwọn tó mọ àdàlù ọtí ṣe dáadáa,+

23 Àwọn tó dá ẹni burúkú láre torí àbẹ̀tẹ́lẹ̀,+

Tí wọn ò sì jẹ́ kí olódodo rí ìdájọ́ òdodo gbà!+

24 Torí náà, bí ahọ́n iná ṣe máa ń jó àgékù pòròpórò run,

Tí koríko gbígbẹ sì máa ń rún sínú ọwọ́ iná,

Gbòǹgbò wọn gangan máa jẹra,

Ìtànná wọn sì máa fọ́n ká bí eruku,

Torí pé wọ́n kọ òfin* Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun,

Wọn ò sì ka ọ̀rọ̀ Ẹni Mímọ́ Ísírẹ́lì sí.+

25 Ìdí nìyẹn tí Jèhófà fi bínú gidigidi sí àwọn èèyàn rẹ̀,

Ó sì máa na ọwọ́ rẹ̀ lòdì sí wọn, ó máa lù wọ́n.+

Àwọn òkè máa mì tìtì,

Òkú wọn sì máa dà bí ààtàn lójú ọ̀nà.+

Pẹ̀lú gbogbo èyí, ìbínú rẹ̀ kò tíì yí pa dà,

Àmọ́ ó ṣì na ọwọ́ rẹ̀ jáde láti lù wọ́n.

26 Ó ti gbé àmì sókè* sí orílẹ̀-èdè tó wà lọ́nà jíjìn;+

Ó ti súfèé sí wọn pé kí wọ́n wá láti àwọn ìkángun ayé;+

Sì wò ó! wọ́n ń yára bọ̀.+

27 Kò rẹ ẹnì kankan nínú wọn, wọn ò sì kọsẹ̀.

Ìkankan nínú wọn ò tòògbé, wọn ò sì sùn.

Àmùrè tó wà ní ìbàdí wọn ò tú,

Okùn bàtà wọn ò sì já.

28 Gbogbo ọfà wọn mú,

Wọ́n sì ti fa gbogbo ọrun wọn.*

Pátákò àwọn ẹṣin wọn dà bí akọ òkúta,

Àwọn àgbá kẹ̀kẹ́ wọn sì dà bí ìjì.+

29 Wọ́n ń ké ramúramù bíi kìnnìún;

Wọ́n ń ké ramúramù bí àwọn ọmọ kìnnìún.*+

Wọ́n máa kùn, wọ́n sì máa mú ẹran,

Wọ́n á gbé e lọ, kò sì ní sẹ́ni tó máa gbà á lọ́wọ́ wọn.

30 Ní ọjọ́ yẹn, wọ́n máa kùn lórí rẹ̀,

Bí òkun ṣe ń ru.+

Òkùnkùn tó ń kó ìdààmú báni ni ẹnikẹ́ni tó bá tẹjú mọ́ ilẹ̀ náà máa rí;

Ìmọ́lẹ̀ pàápàá ti ṣókùnkùn nítorí ìkùukùu.*+

6 Ní ọdún tí Ọba Ùsáyà kú,+ mo rí Jèhófà tó jókòó sórí ìtẹ́ gíga, tó sì ta yọ,+ etí aṣọ rẹ̀ kún inú tẹ́ńpìlì. 2 Àwọn séráfù dúró lókè rẹ̀; ọ̀kọ̀ọ̀kan ní ìyẹ́ mẹ́fà. Ọ̀kọ̀ọ̀kan* fi méjì bo ojú, ó fi méjì bo ẹsẹ̀, ọ̀kọ̀ọ̀kan sì ń fi méjì fò kiri.

 3 Ọ̀kan sì ń sọ fún èkejì pé:

“Mímọ́, mímọ́, mímọ́ ni Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun.+

Ògo rẹ̀ kún gbogbo ayé.”

4 Igbe náà* mú kí ojú ibi tí ilẹ̀kùn ti ń yí mì tìtì, èéfín sì kún ilé náà.+

 5 Mo wá sọ pé: “Mo gbé!

Mo ti kú tán,*

Torí ọkùnrin tí ètè rẹ̀ kò mọ́ ni mí,

Àárín àwọn èèyàn tí ètè wọn ò mọ́ ni mo sì ń gbé;+

Torí ojú mi ti rí Ọba, Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun fúnra rẹ̀!”

6 Ni ọ̀kan lára àwọn séráfù náà bá fò wá sọ́dọ̀ mi, ẹyin iná tó pọ́n yòò+ tó fi ẹ̀mú mú látorí pẹpẹ + sì wà ní ọwọ́ rẹ̀. 7 Ó fi kan ẹnu mi, ó sì sọ pé:

“Wò ó! Ó ti kan ètè rẹ.

Ẹ̀bi rẹ ti kúrò,

A sì ti ṣe ètùtù fún ẹ̀ṣẹ̀ rẹ.”

8 Mo wá gbọ́ ohùn Jèhófà tó sọ pé: “Ta ni kí n rán, ta ló sì máa lọ fún wa?”+ Mo sọ pé: “Èmi nìyí! Rán mi!”+

 9 Ó fèsì pé: “Lọ, kí o sì sọ fún àwọn èèyàn yìí pé:

‘Ẹ máa gbọ́ léraléra,

Àmọ́ kò ní yé yín;

Ẹ máa rí léraléra,

Àmọ́ ẹ ò ní mọ nǹkan kan.’+

10 Mú kí ọkàn àwọn èèyàn yìí yigbì,+

Mú kí etí wọn di,+

Kí o sì lẹ ojú wọn pọ̀,

Kí wọ́n má bàa fi ojú wọn ríran,

Kí wọ́n má sì fi etí wọn gbọ́rọ̀,

Kí ọkàn wọn má bàa lóye,

Kí wọ́n má bàa yí pa dà, kí wọ́n sì rí ìwòsàn.”+

11 Ni mo bá sọ pé: “Títí dìgbà wo, Jèhófà?” Ó dáhùn pé:

“Títí àwọn ìlú náà fi máa fọ́ túútúú, tí kò sì ní sẹ́ni tó ń gbé ibẹ̀,

Tí kò ní sẹ́nì kankan nínú àwọn ilé,

Títí ilẹ̀ náà fi máa pa run, tó sì máa di ahoro;+

12 Títí Jèhófà fi máa mú àwọn èèyàn jìnnà,+

Tí gbogbo ilẹ̀ náà á sì di ahoro.

13 “Àmọ́ ìdá mẹ́wàá ṣì máa wà níbẹ̀, wọ́n á sì tún dáná sun ún, bí igi ńlá àti igi ràgàjì,* tí kùkùté rẹ̀ máa ń ṣẹ́ kù lẹ́yìn tí wọ́n bá gé e; irúgbìn* mímọ́ ló máa jẹ́ kùkùté rẹ̀.”

7 Láyé ìgbà Áhásì+ ọmọ Jótámù ọmọ Ùsáyà, ọba Júdà, Résínì ọba Síríà àti Pékà+ ọmọ Remaláyà, ọba Ísírẹ́lì wá gbógun ja Jerúsálẹ́mù, àmọ́ kò* ṣẹ́gun rẹ̀.+ 2 Ìròyìn dé ilé Dáfídì pé: “Síríà ti lẹ̀dí àpò pọ̀ mọ́ Éfúrémù.”

Jìnnìjìnnì bá ọkàn Áhásì àti ti àwọn èèyàn rẹ̀, wọ́n ń gbọ̀n pẹ̀pẹ̀ bí àwọn igi inú igbó tí atẹ́gùn ń fẹ́ lù.

3 Jèhófà wá sọ fún Àìsáyà pé: “Jọ̀ọ́, jáde lọ pàdé Áhásì, ìwọ àti Ṣeari-jáṣúbù* ọmọ rẹ,+ ní ìpẹ̀kun ibi tí adágún omi tó wà lápá òkè ń gbà,+ níbi ọ̀nà tó lọ sí pápá alágbàfọ̀. 4 Kí o sọ fún un pé, ‘Rí i pé o fi ara rẹ lọ́kàn balẹ̀. Má bẹ̀rù, má sì jẹ́ kí ọkàn rẹ domi torí àwọn ìtì igi méjì tó ń rú èéfín yìí, torí ìbínú Résínì àti Síríà àti ọmọ Remaláyà tó ń ru gùdù.+ 5 Torí Síríà pẹ̀lú Éfúrémù àti ọmọ Remaláyà ti gbìmọ̀ ìkà sí ọ, wọ́n ń sọ pé: 6 “Ẹ jẹ́ ká lọ gbógun ja Júdà, ká fà á ya,* ká ṣẹ́gun rẹ̀* ká gbà á, ká sì fi ọmọ Tábéélì jẹ ọba ibẹ̀.”+

 7 “‘Ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí:

“Kò ní ṣàṣeyọrí,

Kò sì ní ṣẹlẹ̀.

 8 Torí Damásíkù ni orí Síríà,

Résínì sì ni orí Damásíkù.

Kí ọdún márùndínláàádọ́rin (65) tó pé,

Éfúrémù máa fọ́ túútúú, wọn ò sì ní jẹ́ èèyàn mọ́.+

 9 Samáríà+ ni orí Éfúrémù,

Ọmọ Remaláyà sì ni orí Samáríà.+

Tí ìgbàgbọ́ yín ò bá lágbára,

Ẹ ò ní lè fìdí múlẹ̀.”’”

10 Jèhófà ń bá ọ̀rọ̀ tó ń sọ fún Áhásì lọ pé: 11 “Ní kí Jèhófà Ọlọ́run rẹ fún ọ ní àmì kan;+ ó lè jìn bí Isà Òkú,* ó sì lè ga bí ọ̀run.” 12 Àmọ́ Áhásì sọ pé: “Mi ò ní béèrè, mi ò sì ní dán Jèhófà wò.”

13 Àìsáyà wá sọ pé: “Ẹ jọ̀ọ́, ẹ fetí sílẹ̀, ilé Dáfídì. Ṣé bí ẹ ṣe tán àwọn èèyàn ní sùúrù ò tó yín ni? Ṣé ẹ tún fẹ́ tán Ọlọ́run ní sùúrù ni?+ 14 Torí náà, Jèhófà fúnra rẹ̀ máa fún yín ní àmì kan: Wò ó! Ọ̀dọ́bìnrin náà* máa lóyún, ó sì máa bí ọmọkùnrin kan,+ ó máa pe orúkọ rẹ̀ ní Ìmánúẹ́lì.*+ 15 Bọ́tà àti oyin ni á máa jẹ nígbà tó bá fi máa mọ béèyàn ṣe ń kọ ohun búburú, kó sì yan rere. 16 Torí kí ọmọkùnrin náà tó mọ béèyàn ṣe ń kọ ohun búburú, tí á sì yan rere, ilẹ̀ àwọn ọba méjèèjì tí ò ń bẹ̀rù ni wọ́n máa pa tì pátápátá.+ 17 Jèhófà máa mú kí ìgbà kan dé bá ìwọ àtàwọn èèyàn rẹ àti ilé bàbá rẹ, èyí tí kò sí irú rẹ̀ rí láti ọjọ́ tí Éfúrémù ti yapa kúrò lára Júdà,+ torí Ó máa mú ọba Ásíríà wá.+

18 “Ní ọjọ́ yẹn, Jèhófà máa súfèé sí àwọn eṣinṣin láti odò Náílì ti ilẹ̀ Íjíbítì lọ́hùn-ún lọ́hùn-ún àti sí àwọn oyin ilẹ̀ Ásíríà, 19 gbogbo wọn sì máa wá bà lé àwọn àfonífojì tó dà gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́, àwọn pàlàpálá àpáta, gbogbo igi ẹlẹ́gùn-ún àti sórí gbogbo ibi tó lómi.

20 “Ní ọjọ́ yẹn, Jèhófà máa lo abẹ tí wọ́n yá láti agbègbè Odò,* ó máa lo ọba Ásíríà,+ láti fá orí àti irun ẹsẹ̀, ó sì máa fá irùngbọ̀n kúrò pẹ̀lú.

21 “Ní ọjọ́ yẹn, ẹnì kan máa dá ẹ̀mí ọmọ màlúù kan sí látinú ọ̀wọ́ ẹran àti àgùntàn méjì. 22 Torí pé wàrà pọ̀ gan-an, ó máa jẹ bọ́tà; torí gbogbo èèyàn yòókù nílẹ̀ náà máa jẹ bọ́tà àti oyin.

23 “Ní ọjọ́ yẹn, ibikíbi tí ẹgbẹ̀rún (1,000) àjàrà bá wà tẹ́lẹ̀, tí iye rẹ̀ tó ẹgbẹ̀rún (1,000) ẹyọ fàdákà, àwọn igi ẹlẹ́gùn-ún àti èpò nìkan ló máa wà níbẹ̀. 24 Àwọn èèyàn máa mú ọrun àti ọfà lọ síbẹ̀, torí pé igi ẹlẹ́gùn-ún àti èpò ló máa wà ní gbogbo ilẹ̀ náà. 25 Ẹ ò ní lè sún mọ́ gbogbo òkè tí wọ́n ń fi ọkọ́ ro tẹ́lẹ̀, torí pé ẹ ó máa bẹ̀rù àwọn igi ẹlẹ́gùn-ún àti èpò; wọ́n máa di ibi tí àwọn akọ màlúù á ti máa jẹko àti ibi tí àwọn àgùntàn á máa tẹ̀ mọ́lẹ̀.”

8 Jèhófà sọ fún mi pé: “Mú wàláà+ ńlá kan, kí o sì fi kálàmù lásán,* kọ ‘Maheri-ṣalali-háṣí-básì’* sára rẹ̀. 2 Mo fẹ́ rí i dájú pé àwọn ẹlẹ́rìí olóòótọ́ fọwọ́ sí i,* ìyẹn àlùfáà Ùráyà+ àti Sekaráyà ọmọ Jeberekáyà.”

3 Lẹ́yìn náà, mo bá wòlíì obìnrin náà* ní àṣepọ̀,* ó sì lóyún, ó wá bí ọmọkùnrin kan.+ Jèhófà wá sọ fún mi pé: “Sọ ọmọ náà ni Maheri-ṣalali-háṣí-básì, 4 torí kí ọmọ náà tó mọ bí wọ́n ṣe ń pe, ‘Bàbá mi!’ àti ‘Ìyá mi!’ wọ́n máa kó àwọn ohun àmúṣọrọ̀ Damásíkù àti ẹrù ogun Samáríà lọ níwájú ọba Ásíríà.”+

5 Jèhófà tún sọ fún mi pé:

 6 “Torí pé àwọn èèyàn yìí ti pa omi Ṣílóà* tó rọra ń ṣàn tì,+

Tí wọ́n sì ń yọ̀ torí Résínì àti ọmọ Remaláyà,+

 7 Torí náà, wò ó! Jèhófà máa mú kí

Ibú omi Odò ńlá* náà ya lù wọ́n,

Ọba Ásíríà+ àti gbogbo ògo rẹ̀.

Ó máa wá sórí gbogbo ibi tí omi rẹ̀ ń ṣàn gbà,

Ó máa kún bo gbogbo bèbè rẹ̀,

 8 Ó sì máa rọ́ gba Júdà kọjá.

Ó máa kún bò ó, ó sì máa gbà á kọjá, ó máa kún dé ọrùn rẹ̀;+

Ìyẹ́ rẹ̀ tó nà jáde máa bo ìbú ilẹ̀ rẹ,

Ìwọ Ìmánúẹ́lì!”*+

 9 Ẹ ṣe wọ́n léṣe, ẹ̀yin èèyàn, àmọ́ a máa fọ́ ẹ̀yin náà sí wẹ́wẹ́.

Ẹ fetí sílẹ̀, gbogbo ẹ̀yin tí ẹ wá láti apá ibi tó jìnnà ní ayé!

Ẹ múra ogun,* àmọ́ a máa fọ́ yín sí wẹ́wẹ́!+

Ẹ múra ogun, àmọ́ a máa fọ́ yín sí wẹ́wẹ́!

10 Ẹ gbìmọ̀ pọ̀, àmọ́ a máa dà á rú!

Ẹ sọ ohun tó wù yín, àmọ́ kò ní yọrí sí rere,

Torí Ọlọ́run wà pẹ̀lú wa!*+

11 Pẹ̀lú ọwọ́ agbára rẹ̀ lára mi, ohun tí Jèhófà sọ fún mi nìyí, láti kìlọ̀ fún mi kí n má bàa tẹ̀ lé ọ̀nà àwọn èèyàn yìí:

12 “Tí àwọn èèyàn yìí bá ń pe nǹkan ní ọ̀tẹ̀, ẹ ò gbọ́dọ̀ pè é ní ọ̀tẹ̀!

Ẹ má bẹ̀rù ohun tí wọ́n bẹ̀rù;

Ẹ má ṣe jẹ́ kó kó jìnnìjìnnì bá yín.

13 Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun ni Ẹni tó yẹ kí ẹ kà sí mímọ́,+

Òun ni Ẹni tó yẹ kí ẹ bẹ̀rù,

Òun sì ni Ẹni tó yẹ kó mú kí ẹ gbọ̀n jìnnìjìnnì.”+

14 Ó máa dà bí ibi mímọ́,

Àmọ́ ó máa dà bí òkúta tí wọ́n á kọ lù

Àti àpáta tó ń múni kọsẹ̀+

Fún ilé Ísírẹ́lì méjèèjì,

Bíi pańpẹ́ àti ìdẹkùn,

Fún àwọn tó ń gbé Jerúsálẹ́mù.

15 Ọ̀pọ̀ nínú wọn máa kọsẹ̀, wọ́n á ṣubú, wọ́n á sì fọ́;

Wọ́n máa dẹkùn fún wọn, ọwọ́ á sì tẹ̀ wọ́n.

16 Ká ẹ̀rí tó wà lákọsílẹ̀;*

Gbé èdìdì lé òfin* náà láàárín àwọn ọmọ ẹ̀yìn mi!

17 Màá máa dúró de* Jèhófà,+ ẹni tó ń fi ojú rẹ̀ pa mọ́ fún ilé Jékọ́bù,+ màá sì ní ìrètí nínú rẹ̀.

18 Wò ó! Èmi àti àwọn ọmọ tí Jèhófà fún mi+ dà bí àmì+ àti iṣẹ́ ìyanu ní Ísírẹ́lì látọ̀dọ̀ Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun, ẹni tó ń gbé lórí Òkè Síónì.

19 Tí wọ́n bá sì sọ fún yín pé: “Ẹ lọ wádìí lọ́wọ́ àwọn abẹ́mìílò tàbí àwọn woṣẹ́woṣẹ́, àwọn tó ń ké ṣíoṣío, tí wọ́n sì ń jẹnu wúyẹ́wúyẹ́,” ṣebí ọwọ́ Ọlọ́run wọn ló yẹ kí àwọn èèyàn ti lọ wádìí? Ṣé ó yẹ kí wọ́n lọ wádìí ọ̀rọ̀ lọ́wọ́ òkú nítorí alààyè?+ 20 Kàkà bẹ́ẹ̀, inú òfin àti ẹ̀rí tó wà ní àkọsílẹ̀* ló yẹ kí wọ́n ti wádìí!

Tí wọn ò bá sọ ohun tó bá ọ̀rọ̀ yìí mu, wọn ò ní ìmọ́lẹ̀.*+ 21 Kálukú máa gba ilẹ̀ náà kọjá, ìyà á jẹ wọ́n, ebi á sì pa wọ́n;+ torí ebi tó ń pa á àti inú tó ń bí i, á máa gégùn-ún fún ọba rẹ̀ àti Ọlọ́run rẹ̀ bó ṣe ń wòkè. 22 Ó máa wá wo ayé, ìdààmú àti òkùnkùn nìkan ló sì máa rí, ìríran bàìbàì àti àkókò tó le, ìṣúdùdù, láìsí ìmọ́lẹ̀.

9 Àmọ́, ìṣúdùdù náà kò ní rí bí ìgbà tí ìdààmú bá ilẹ̀ náà, bí ìgbà àtijọ́ tí wọ́n hùwà àbùkù sí ilẹ̀ Sébúlúnì àti ilẹ̀ Náfútálì.+ Àmọ́ tó bá yá, Ó máa mú kí a bọlá fún un, ní ọ̀nà ibi òkun, ní agbègbè Jọ́dánì, Gálílì àwọn orílẹ̀-èdè.

 2 Àwọn èèyàn tó ń rìn nínú òkùnkùn

Ti rí ìmọ́lẹ̀ tó mọ́lẹ̀ yòò.

Ní ti àwọn tó ń gbé ilẹ̀ tó ṣókùnkùn biribiri,

Ìmọ́lẹ̀ ti tàn sórí wọn.+

 3 O ti sọ orílẹ̀-èdè náà di púpọ̀;

O ti mú kó máa yọ̀ gidigidi.

Wọ́n ń yọ̀ níwájú rẹ

Bí àwọn èèyàn ṣe ń yọ̀ nígbà ìkórè,

Bí àwọn tó ń fayọ̀ pín ẹrù ogun.

 4 Torí o ti fọ́ àjàgà ẹrù wọn sí wẹ́wẹ́,

Ọ̀pá tó wà ní èjìká wọn, ọ̀pá ẹni tó ń kó wọn ṣiṣẹ́,

Bíi ti ọjọ́ Mídíánì.+

 5 Gbogbo bàtà tó ń kilẹ̀ bó ṣe ń lọ

Àti gbogbo aṣọ tí wọ́n rì bọnú ẹ̀jẹ̀

Ló máa di ohun tí wọ́n fi ń dá iná.

 6 Torí a ti bí ọmọ kan fún wa,+

A ti fún wa ní ọmọkùnrin kan;

Àkóso* sì máa wà ní èjìká rẹ̀.+

Orúkọ rẹ̀ á máa jẹ́ Àgbàyanu Agbani-nímọ̀ràn,+ Ọlọ́run Alágbára,+ Baba Ayérayé, Ọmọ Aládé Àlàáfíà.

 7 Àkóso* rẹ̀ á máa gbilẹ̀ títí lọ,

Àlàáfíà kò sì ní lópin,+

Lórí ìtẹ́ Dáfídì+ àti lórí ìjọba rẹ̀,

Kó lè fìdí rẹ̀ múlẹ̀ gbọn-in,+ kó sì gbé e ró,

Nípasẹ̀ ìdájọ́+ tí ó tọ́ àti òdodo,+

Láti ìsinsìnyí lọ àti títí láé.

Ìtara Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun máa ṣe èyí.

 8 Jèhófà fi ọ̀rọ̀ kan ránṣẹ́ sí Jékọ́bù,

Ó sì ti wá sórí Ísírẹ́lì.+

 9 Gbogbo èèyàn sì máa mọ̀ ọ́n,

Éfúrémù àti àwọn tó ń gbé ní Samáríà,

Tí wọ́n ń fi ìgbéraga àti àfojúdi ọkàn sọ pé:

10 “Àwọn bíríkì ti wó,

Àmọ́ òkúta tí wọ́n gbẹ́ la máa fi kọ́lé.+

Wọ́n ti gé àwọn igi síkámórè lulẹ̀,

Àmọ́ á máa fi àwọn igi kédárì rọ́pò wọn.”

11 Jèhófà máa gbé àwọn elénìní Résínì dìde sí i,

Ó sì máa ru àwọn ọ̀tá rẹ̀ sókè láti jagun,

12 Síríà láti ìlà oòrùn àti àwọn Filísínì láti ìwọ̀ oòrùn,*+

Wọ́n máa la ẹnu wọn, wọ́n á sì jẹ Ísírẹ́lì run.+

Pẹ̀lú gbogbo èyí, ìbínú rẹ̀ kò tíì yí pa dà,

Àmọ́ ó ṣì na ọwọ́ rẹ̀ jáde láti lù wọ́n.+

13 Torí àwọn èèyàn náà kò tíì pa dà sọ́dọ̀ Ẹni tó ń lù wọ́n;

Wọn ò wá Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun.+

14 Jèhófà máa gé orí àti ìrù, ọ̀mùnú àti koríko etídò*

Kúrò ní Ísírẹ́lì, ní ọjọ́ kan ṣoṣo.+

15 Àgbà ọkùnrin àti ẹni tí àwọn èèyàn bọ̀wọ̀ fún gidigidi ni orí,

Wòlíì tó ń fúnni ní ìtọ́ni èké sì ni ìrù.+

16 Àwọn tó ń darí àwọn èèyàn yìí ń mú kí wọ́n rìn gbéregbère,

Nǹkan sì ti dà rú mọ́ àwọn tó ń tẹ̀ lé wọn lójú.

17 Ìdí nìyẹn tí inú Jèhófà ò fi ní dùn sí àwọn ọ̀dọ́kùnrin wọn,

Kò sì ní ṣàánú àwọn ọmọ aláìníbaba* àti àwọn opó wọn

Torí apẹ̀yìndà àti aṣebi ni gbogbo wọn,+

Gbogbo ẹnu sì ń sọ ọ̀rọ̀ òpònú.

Pẹ̀lú gbogbo èyí, ìbínú rẹ̀ kò tíì yí pa dà,

Àmọ́ ó ṣì na ọwọ́ rẹ̀ jáde láti lù wọ́n.+

18 Torí pé ìwà burúkú máa ń jó bí iná,

Ó ń jó àwọn igi ẹlẹ́gùn-ún àti èpò run.

Ó máa dáná sí igbó tó díjú,

Èéfín wọn tó ṣú sì máa ròkè lálá.

19 Torí ìbínú Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun,

A ti dáná sí ilẹ̀ náà,

Wọ́n á sì fi àwọn èèyàn náà dáná.

Ẹnì kankan ò ní dá ẹ̀mí arákùnrin rẹ̀ pàápàá sí.

20 Ẹnì kan máa gé nǹkan lulẹ̀ ní ọwọ́ ọ̀tún,

Àmọ́ ebi á ṣì máa pa á;

Ẹnì kan sì máa jẹun ní ọwọ́ òsì,

Àmọ́ kò ní yó.

Kálukú máa jẹ ẹran apá rẹ̀,

21 Mánásè máa jẹ Éfúrémù run,

Éfúrémù sì máa jẹ Mánásè run.

Wọ́n máa para pọ̀ gbéjà ko Júdà.+

Pẹ̀lú gbogbo èyí, ìbínú rẹ̀ kò tíì yí pa dà,

Àmọ́ ó ṣì na ọwọ́ rẹ̀ jáde láti lù wọ́n.+

10 Àwọn tó ń gbé ìlànà tó ń pani lára kalẹ̀ gbé,+

Àwọn tó ń ṣe òfin tó ń nini lára ṣáá,

 2 Láti fi ẹ̀tọ́ àwọn aláìní dù wọ́n lábẹ́ òfin,

Láti fi ìdájọ́ òdodo du àwọn tó rẹlẹ̀ láàárín àwọn èèyàn mi,+

Wọ́n ń kó àwọn opó nífà bí ẹrù ogun

Àti àwọn ọmọ aláìníbaba* bí ẹrù tí wọ́n kó lójú ogun!+

 3 Kí lẹ máa ṣe ní ọjọ́ ìjíhìn,*+

Tí ìparun bá wá láti ọ̀nà jíjìn?+

Ta lẹ máa sá lọ bá pé kó ràn yín lọ́wọ́,+

Ibo lẹ sì máa fi ọrọ̀* yín sí?

 4 Kò sí ohun tó ṣẹ́ kù ju pé kí ẹ bẹ̀rẹ̀ sáàárín àwọn ẹlẹ́wọ̀n

Tàbí kí ẹ ṣubú láàárín àwọn tí wọ́n pa.

Pẹ̀lú gbogbo èyí, ìbínú rẹ̀ kò tíì yí pa dà,

Àmọ́ ó ṣì na ọwọ́ rẹ̀ jáde láti lù wọ́n.+

 5 “Àháà! ará Ásíríà,+

Ọ̀pá tí mo fi ń fi ìbínú mi hàn+

Àti ọ̀pá ọwọ́ wọn tí mo fi ń báni wí!

 6 Màá rán an sí orílẹ̀-èdè apẹ̀yìndà,+

Sí àwọn èèyàn tó múnú bí mi;

Màá pàṣẹ fún un pé kó kó nǹkan púpọ̀ àti ẹrù ogun tó pọ̀,

Kó sì tẹ̀ wọ́n mọ́lẹ̀ bí ẹrẹ̀ lójú ọ̀nà.+

 7 Àmọ́ kò ní fẹ́ ṣe bẹ́ẹ̀,

Kò sì ní gbèrò lọ́kàn rẹ̀ láti ṣe bẹ́ẹ̀;

Torí ó wà lọ́kàn rẹ̀ láti pani run,

Láti pa ọ̀pọ̀lọpọ̀ orílẹ̀-èdè rẹ́, tí kì í ṣe díẹ̀.

 8 Torí ó sọ pé,

‘Ṣebí ọba ni gbogbo àwọn ìjòyè mi?+

 9 Ṣebí bíi Kákémíṣì+ gẹ́lẹ́ ni Kálínò+ rí?

Ṣebí Hámátì+ rí bí Áápádì?+

Ṣebí bíi Damásíkù+ ni Samáríà+ rí?

10 Ọwọ́ mi tẹ ìjọba àwọn ọlọ́run tí kò ní láárí,

Àwọn tí ère gbígbẹ́ wọn pọ̀ ju ti Jerúsálẹ́mù àti Samáríà lọ!+

11 Ǹjẹ́ kì í ṣe ohun tí mo ṣe sí Samáríà àti àwọn ọlọ́run rẹ̀ tí kò ní láárí gẹ́lẹ́

Ni màá ṣe sí Jerúsálẹ́mù àti àwọn òrìṣà rẹ̀?’+

12 “Tí Jèhófà bá ti parí gbogbo iṣẹ́ rẹ̀ lórí Òkè Síónì àti ní Jerúsálẹ́mù, Ó* máa fìyà jẹ ọba Ásíríà torí àfojúdi ọkàn rẹ̀ àti ojú rẹ̀ gíga tó fi ń woni pẹ̀lú ìgbéraga.+ 13 Torí ó sọ pé,

‘Agbára ọwọ́ mi ni màá fi ṣe èyí

Àti ọgbọ́n mi, torí mo gbọ́n.

Màá mú ààlà àwọn èèyàn kúrò,+

Màá sì kó àwọn ìṣúra wọn,+

Bí alágbára ni màá kápá àwọn tó ń gbé ibẹ̀.+

14 Bí èèyàn tó fẹ́ tọwọ́ bọ ìtẹ́ ẹyẹ,

Ọwọ́ mi máa tẹ àwọn ohun àmúṣọrọ̀ àwọn èèyàn;

Bí ẹni tó sì ń kó ẹyin tí wọ́n pa tì jọ,

Ni màá kó gbogbo ayé jọ!

Kò sẹ́ni tó máa gbọn ìyẹ́ rẹ̀, tó máa la ẹnu tàbí tó máa ké ṣíoṣío.’”

15 Ṣé àáké máa gbé ara rẹ̀ ga ju ẹni tó ń fi gé nǹkan?

Ṣé ayùn máa gbé ara rẹ̀ ga ju ẹni tó ń fi rẹ́ nǹkan?

Ṣé ọ̀pá+ lè fi ẹni tó gbé e sókè?

Àbí ọ̀pá lè gbé ẹni tí wọn ò fi igi ṣe sókè?

16 Torí náà, Olúwa tòótọ́, Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun

Máa mú kí àwọn èèyàn rẹ̀ tó sanra rù,+

Ó sì máa dá iná tó ń jó lala sábẹ́ ògo rẹ̀.+

17 Ìmọ́lẹ̀ Ísírẹ́lì+ máa di iná,+

Ẹni Mímọ́ rẹ̀ sì máa di ọwọ́ iná;

Ó máa jó àwọn èpò àtàwọn igi ẹlẹ́gùn-ún rẹ̀ run ní ọjọ́ kan.

18 Ó máa mú ògo igbó rẹ̀ àti ọgbà eléso rẹ̀ kúrò pátápátá;*

Ó máa dà bí ìgbà tí ẹni tó ń ṣàìsàn ń kú lọ.+

19 Iye igi tó kù nínú igbó rẹ̀

Máa kéré gan-an débi pé ọmọdékùnrin máa lè kọ iye wọn sílẹ̀.

20 Ní ọjọ́ yẹn, àwọn tó ṣẹ́ kù ní Ísírẹ́lì

Àti àwọn tó yè bọ́ ní ilé Jékọ́bù

Kò tún ní gbára lé ẹni tó lù wọ́n;+

Àmọ́ wọ́n máa fi òtítọ́ gbára lé Jèhófà,

Ẹni Mímọ́ Ísírẹ́lì.

21 Àṣẹ́kù nìkan ló máa pa dà,

Àṣẹ́kù Jékọ́bù, sọ́dọ̀ Ọlọ́run Alágbára.+

22 Ìwọ Ísírẹ́lì, bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn èèyàn rẹ

Pọ̀ bí iyanrìn òkun,

Àṣẹ́kù wọn nìkan ló máa pa dà.+

A ti pinnu ìparun ráúráú,+

Ìdájọ́ òdodo* sì máa bò wọ́n.+

23 Àní, ìparun ráúráú tí Olúwa Ọba Aláṣẹ, Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun pinnu,

Máa ṣẹlẹ̀ ní gbogbo ilẹ̀ náà.+

24 Torí náà, ohun tí Olúwa Ọba Aláṣẹ, Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun sọ nìyí: “Ẹ̀yin èèyàn mi tó ń gbé ní Síónì, ẹ má bẹ̀rù nítorí ará Ásíríà tó ti máa ń fi ọ̀pá lù yín,+ tó sì máa ń gbé ọ̀pá rẹ̀ sókè sí yín bíi ti Íjíbítì.+ 25 Torí kò ní pẹ́ rárá tí ìbáwí náà fi máa dópin; ìbínú mi máa mú kí n pa wọ́n run.+ 26 Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun máa yọ pàṣán kan sí i,+ bó ṣe ṣe nígbà tó ṣẹ́gun Mídíánì lẹ́gbẹ̀ẹ́ àpáta Órébù.+ Ọ̀pá rẹ̀ máa wà lórí òkun, ó sì máa nà á sókè bó ṣe ṣe sí Íjíbítì.+

27 Ní ọjọ́ yẹn, ẹrù rẹ̀ máa kúrò ní èjìká rẹ+

Àti àjàgà rẹ̀ kúrò ní ọrùn rẹ,+

Àjàgà náà sì máa ṣẹ́+ torí òróró.”

28 Ó ti wá sí Áyátì;+

Ó ti gba Mígírónì kọjá;

Míkímáṣì+ ló kó ẹrù rẹ̀ sí.

29 Wọ́n ti kọjá níbi tó ṣeé fẹsẹ̀ gbà nínú odò;

Gébà+ ni wọ́n sùn mọ́jú;

Rámà gbọ̀n rìrì, Gíbíà + ti Sọ́ọ̀lù ti sá lọ.+

30 Kígbe kí o sì pariwo, ìwọ ọmọbìnrin Gálímù!

Fiyè sílẹ̀, ìwọ Láíṣà!

O gbé, ìwọ Ánátótì!+

31 Mádíménà ti sá lọ.

Àwọn tó ń gbé Gébímù ti wá ibì kan fara pa mọ́ sí.

32 Lónìí yìí gan-an, ó máa dúró ní Nóbù.+

Ó mi ẹ̀ṣẹ́ rẹ̀ sí òkè ọmọbìnrin Síónì,

Òkè kékeré Jerúsálẹ́mù.

33 Wò ó! Olúwa tòótọ́, Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun,

Ń gé àwọn ẹ̀ka lulẹ̀, bí wọ́n ṣe ń fọ́ yángá sì bani lẹ́rù;+

Ó ń gé àwọn igi tó ga jù lulẹ̀,

Ó sì ń rẹ àwọn tó ta yọ wálẹ̀.

34 Ó ń fi irinṣẹ́ onírin* ṣá igbó tó díjú balẹ̀,

Lẹ́bánónì sì máa ti ọwọ́ alágbára kan ṣubú.

11 Ẹ̀ka igi+ kan máa yọ látinú kùkùté Jésè,+

Èéhù+ kan látinú gbòǹgbò rẹ̀ sì máa so èso.

 2 Ẹ̀mí Jèhófà máa bà lé e,+

Ẹ̀mí ọgbọ́n+ àti ti òye,

Ẹ̀mí ìmọ̀ràn àti ti agbára,+

Ẹ̀mí ìmọ̀ àti ti ìbẹ̀rù Jèhófà.

 3 Ìbẹ̀rù Jèhófà máa jẹ́ ìdùnnú rẹ̀.+

Kò ní gbé ìdájọ́ rẹ̀ ka ohun tó fojú rí,

Kò sì ní gbé ìbáwí rẹ̀ ka ohun tó fetí gbọ́ lásán.+

 4 Ó máa dá ẹjọ́ àwọn ẹni rírẹlẹ̀ bó ṣe tọ́,*

Ó sì máa fi òtítọ́ báni wí torí àwọn oníwà pẹ̀lẹ́ tó wà ní ayé.

Ó máa fi ọ̀pá ẹnu rẹ̀ lu ayé,+

Ó sì máa fi èémí* ètè rẹ̀ pa ẹni burúkú.+

 5 Òdodo ló máa jẹ́ àmùrè ìgbáròkó rẹ̀,

Òtítọ́ ló sì máa jẹ́ àmùrè ìbàdí rẹ̀.+

 6 Ìkookò máa bá ọ̀dọ́ àgùntàn gbé fúngbà díẹ̀,+

Àmọ̀tẹ́kùn máa dùbúlẹ̀ ti ọmọ ewúrẹ́,

Ọmọ màlúù, kìnnìún* àti ẹran tó sanra á jọ wà pa pọ̀;*+

Ọmọ kékeré á sì máa dà wọ́n.

 7 Màlúù àti bíárì á jọ máa jẹun,

Àwọn ọmọ wọn á sì jọ dùbúlẹ̀.

Kìnnìún máa jẹ pòròpórò bí akọ màlúù.+

 8 Ọmọ ẹnu ọmú máa ṣeré lórí ihò ṣèbé,

Ọmọ tí wọ́n ti gba ọmú lẹ́nu rẹ̀ sì máa fọwọ́ sí ihò ejò olóró.

 9 Wọn ò ní fa ìpalára kankan,+

Tàbí ìparun kankan ní gbogbo òkè mímọ́ mi,+

Torí ó dájú pé ìmọ̀ Jèhófà máa bo ayé,

Bí omi ṣe ń bo òkun.+

10 Ní ọjọ́ yẹn, gbòǹgbò Jésè+ máa dúró bí àmì* fún àwọn èèyàn.+

Ọ̀dọ̀ rẹ̀ ni àwọn orílẹ̀-èdè máa yíjú sí fún ìtọ́sọ́nà,*+

Ibi ìsinmi rẹ̀ sì máa di ológo.

11 Ní ọjọ́ yẹn, Jèhófà tún máa na ọwọ́ rẹ̀ lẹ́ẹ̀kejì, láti gba àṣẹ́kù àwọn èèyàn rẹ̀ pa dà, àwọn tó ṣẹ́ kù láti Ásíríà,+ Íjíbítì,+ Pátírọ́sì,+ Kúṣì,+ Élámù,+ Ṣínárì,* Hámátì àti àwọn erékùṣù òkun.+ 12 Ó máa gbé àmì* kan sókè fún àwọn orílẹ̀-èdè, ó sì máa kó àwọn tó fọ́n ká lára Ísírẹ́lì jọ,+ ó máa kó àwọn tó tú ká lára Júdà jọ láti ìkángun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ayé.+

13 Owú Éfúrémù máa pòórá,+

Àwọn tó sì ń fi ẹ̀tanú hàn sí Júdà máa pa run.

Éfúrémù ò ní jowú Júdà,

Júdà ò sì ní fi ẹ̀tanú hàn sí Éfúrémù.+

14 Wọ́n máa já ṣòòrò wálẹ̀ sí gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́* àwọn Filísínì lápá ìwọ̀ oòrùn;

Wọ́n jọ máa kó ẹrù àwọn ará Ìlà Oòrùn.

Wọ́n máa na ọwọ́ wọn sí* Édómù+ àti Móábù,+

Àwọn ọmọ Ámónì sì máa di ọmọ abẹ́ wọn.+

15 Jèhófà máa pín* ibi tí òkun Íjíbítì ti ya wọ ilẹ̀,*+

Ó sì máa fi ọwọ́ rẹ̀ lórí Odò.*+

Ó máa fi èémí* rẹ̀ tó ń jó nǹkan gbẹ kọ lu ọ̀gbàrá rẹ̀ méjèèje,*

Ó sì máa mú kí àwọn èèyàn fi bàtà wọn rìn kọjá.

16 Ọ̀nà kan sì máa jáde+ láti Ásíríà fún àṣẹ́kù àwọn èèyàn rẹ̀ yòókù,+

Bó ṣe rí fún Ísírẹ́lì ní ọjọ́ tó kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì.

12 Ní ọjọ́ yẹn, ó dájú pé o máa sọ pé:

“Mo dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ, Jèhófà,

Torí bó tiẹ̀ jẹ́ pé o bínú sí mi,

Ìbínú rẹ ti wá rọlẹ̀, o sì tù mí nínú.+

 2 Wò ó! Ọlọ́run ni ìgbàlà mi.+

Màá gbẹ́kẹ̀ lé e, ẹ̀rù ò sì ní bà mí;+

Torí Jáà* Jèhófà ni okun mi àti agbára mi,

Ó sì ti wá di ìgbàlà mi.”+

 3 Tayọ̀tayọ̀ lẹ máa fa omi

Látinú àwọn ìsun ìgbàlà.+

 4 Ní ọjọ́ yẹn, ẹ máa sọ pé:

“Ẹ fi ọpẹ́ fún Jèhófà, ẹ ké pe orúkọ rẹ̀,

Ẹ jẹ́ kí àwọn èèyàn mọ àwọn ohun tí ó ṣe!+

Ẹ kéde pé a ti gbé orúkọ rẹ̀ ga.+

 5 Ẹ kọrin ìyìn sí* Jèhófà,+ torí ó ti ṣe àwọn ohun tó yani lẹ́nu.+

Ẹ jẹ́ kí gbogbo ayé mọ èyí.

 6 Ké jáde, kí o sì kígbe ayọ̀, ìwọ* tó ń gbé ní Síónì,

Torí Ẹni Mímọ́ Ísírẹ́lì tóbi láàárín rẹ.”

13 Ọ̀rọ̀ ìkéde sí Bábílónì,+ tí Àìsáyà+ ọmọ Émọ́ọ̀sì rí nínú ìran:

 2 “Ẹ gbé àmì kan*+ sókè lórí òkè tó jẹ́ kìkì àpáta.

Ẹ ké pè wọ́n, ẹ ju ọwọ́,

Kí wọ́n lè wá sí ẹnu ọ̀nà àwọn èèyàn pàtàkì.

 3 Mo ti pàṣẹ fún àwọn tí mo yàn.*+

Mo ti ké sí àwọn jagunjagun mi pé kí wọ́n fi ìbínú mi hàn,

Àwọn èèyàn mi tó ń yangàn, tí wọ́n sì ń yọ̀.

 4 Fetí sílẹ̀! Ọ̀pọ̀ èèyàn wà lórí òkè;

Ìró wọn dà bí ìró ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ èèyàn!

Fetí sílẹ̀! Ariwo àwọn ìjọba,

Ti àwọn orílẹ̀-èdè tó kóra jọ!+

Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun ń pe àwọn ọmọ ogun jọ.+

 5 Wọ́n ń bọ̀ láti ilẹ̀ tó jìnnà,+

Láti ìkángun ọ̀run,

Jèhófà àti àwọn ohun ìjà ìbínú rẹ̀,

Láti pa gbogbo ayé run.+

 6 Ẹ pohùn réré ẹkún, torí ọjọ́ Jèhófà sún mọ́lé!

Ó máa jẹ́ ọjọ́ ìparun látọ̀dọ̀ Olódùmarè.+

 7 Ìdí nìyẹn tí gbogbo ọwọ́ fi máa rọ,

Tí ìbẹ̀rù sì máa mú kí ọkàn gbogbo èèyàn domi.+

 8 Jìnnìjìnnì bo àwọn èèyàn náà.+

Iṣan wọn sún kì, wọ́n sì ń jẹ̀rora,

Bí obìnrin tó ń rọbí.

Wọ́n ń wo ara wọn tìbẹ̀rù-tìbẹ̀rù,

Ìrora sì hàn lójú wọn.

 9 Wò ó! Ọjọ́ Jèhófà ń bọ̀,

Ọjọ́ tó lágbára pẹ̀lú ìbínú tó le àti ìbínú tó ń jó fòfò,

Láti sọ ilẹ̀ náà di ohun àríbẹ̀rù,+

Kó sì pa àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ ilẹ̀ náà run kúrò lórí rẹ̀.

10 Torí àwọn ìràwọ̀ ojú ọ̀run àti àwọn àgbájọ ìràwọ̀ wọn*+

Kò ní tan ìmọ́lẹ̀ wọn jáde;

Oòrùn máa ṣókùnkùn tó bá ràn,

Òṣùpá ò sì ní tan ìmọ́lẹ̀ rẹ̀.

11 Màá pe àwọn tó ń gbé ayé lẹ́jọ́ torí ìwà burúkú wọn,+

Màá sì pe àwọn ẹni burúkú lẹ́jọ́ torí ẹ̀ṣẹ̀ wọn.

Màá fòpin sí ìyangàn àwọn agbéraga,

Màá sì rẹ ìgbéraga àwọn oníwà ìkà wálẹ̀.+

12 Màá mú kí ẹni kíkú ṣọ̀wọ́n ju wúrà tí wọ́n yọ́ mọ́,+

Màá sì mú kí àwọn èèyàn ṣọ̀wọ́n ju wúrà Ófírì.+

13 Ìdí nìyẹn tí màá fi mú kí ọ̀run gbọ̀n rìrì,

Ayé sì máa mì jìgìjìgì kúrò ní àyè rẹ̀+

Nígbà tí Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun bá bínú gidigidi ní ọjọ́ ìbínú rẹ̀ tó ń jó bí iná.

14 Bí egbin tí wọ́n ń dọdẹ àti bí agbo ẹran tí kò sí ẹnikẹ́ni tó máa kó wọn jọ,

Kálukú máa pa dà sọ́dọ̀ àwọn èèyàn rẹ̀;

Kálukú sì máa sá lọ sí ilẹ̀ rẹ̀.+

15 Wọ́n máa gún ẹnikẹ́ni tí wọ́n bá rí ní àgúnyọ,

Wọ́n sì máa fi idà pa ẹnikẹ́ni tí wọ́n bá mú.+

16 Wọ́n máa já àwọn ọmọ wọn sí wẹ́wẹ́ níṣojú wọn,+

Wọ́n máa kó ẹrù ilé wọn,

Wọ́n sì máa fipá bá àwọn ìyàwó wọn lò pọ̀.

17 Màá gbé àwọn ará Mídíà dìde sí wọn,+

Àwọn tí kò ka fàdákà sí nǹkan kan,

Tí wúrà ò sì já mọ́ nǹkan kan lójú wọn.

18 Ọfà wọn máa run àwọn ọ̀dọ́kùnrin túútúú;+

Wọn ò ní káàánú èso ikùn,

Wọn ò sì ní ṣàánú àwọn ọmọdé.

19 Bábílónì tó lógo* jù nínú àwọn ìjọba,+

Ẹwà àti ògo àwọn ará Kálídíà,+

Máa dà bíi Sódómù àti Gòmórà nígbà tí Ọlọ́run bì wọ́n ṣubú.+

20 Ẹnikẹ́ni ò ní gbé inú rẹ̀ mọ́ láé,

Kò sì sẹ́ni tó máa gbé ibẹ̀ láti ìran dé ìran.+

Ará Arébíà kankan ò ní pàgọ́ síbẹ̀,

Olùṣọ́ àgùntàn kankan ò sì ní jẹ́ kí agbo ẹran rẹ̀ sinmi níbẹ̀.

21 Àwọn ẹranko inú aṣálẹ̀ máa dùbúlẹ̀ síbẹ̀;

Àwọn ẹyẹ òwìwí máa kún ilé wọn.

Àwọn ògòǹgò á máa gbé ibẹ̀,+

Àwọn ewúrẹ́ igbó* á máa tọ kiri níbẹ̀.

22 Àwọn ẹranko tó ń hu á máa ké nínú àwọn ilé gogoro rẹ̀

Àti àwọn ajáko* nínú àwọn ààfin rẹ̀ tó lọ́lá.

Àkókò rẹ̀ ti sún mọ́lé, a ò sì ní fi kún àwọn ọjọ́ rẹ̀.”+

14 Torí Jèhófà máa ṣàánú Jékọ́bù,+ ó sì máa tún Ísírẹ́lì yàn.+ Ó máa mú kí wọ́n gbé* ní ilẹ̀ wọn,+ àwọn àjèjì máa dara pọ̀ mọ́ wọn, wọ́n sì máa sọ ara wọn di ará ilé Jékọ́bù.+ 2 Àwọn èèyàn máa mú wọn, wọ́n á mú wọn wá sí àyè wọn, ilé Ísírẹ́lì sì máa fi wọ́n ṣe ẹrúkùnrin àti ẹrúbìnrin+ ní ilẹ̀ Jèhófà; wọ́n máa mú àwọn tó mú wọn lẹ́rú, wọ́n sì máa di olórí àwọn tó fipá kó wọn ṣiṣẹ́.

3 Ní ọjọ́ tí Jèhófà bá mú kí o bọ́ nínú ìrora rẹ, rúkèrúdò rẹ àti bí wọ́n ṣe ń fipá mú ọ sìnrú,+ 4 o máa pa òwe* yìí sí ọba Bábílónì pé:

“Ẹ wo bí òpin ṣe dé bá ẹni tó ń fipá kó àwọn míì ṣiṣẹ́!

Ẹ wo bí ìfìyàjẹni ṣe wá sí òpin!+

 5 Jèhófà ti kán ọ̀pá àwọn ẹni burúkú,

Ọ̀pá àwọn tó ń ṣàkóso,+

 6 Ẹni tó ń fìbínú kan àwọn èèyàn lẹ́ṣẹ̀ẹ́ láìdáwọ́ dúró,+

Ẹni tó ń fi ìkannú tẹ àwọn orílẹ̀-èdè lórí ba, tó sì ń ṣe inúnibíni sí wọn láìṣíwọ́.+

 7 Gbogbo ayé ti wá sinmi, ó bọ́ lọ́wọ́ ìyọlẹ́nu.

Àwọn èèyàn ń kígbe ayọ̀.+

 8 Àwọn igi júnípà pàápàá ń yọ̀ torí rẹ,

Pẹ̀lú àwọn igi kédárì Lẹ́bánónì.

Wọ́n sọ pé, ‘Látìgbà tí o ti ṣubú,

Kò sí agégi kankan tó dìde sí wa.’

 9 Isà Òkú* tó wà nísàlẹ̀ pàápàá ti ru sókè,

Láti pàdé rẹ tí o bá dé.

Nítorí rẹ, ó jí àwọn tí ikú ti pa,*

Gbogbo àwọn aṣáájú ayé tó ń fìyà jẹni.*

Ó ń mú kí gbogbo ọba àwọn orílẹ̀-èdè dìde lórí ìtẹ́ wọn.

10 Gbogbo wọn sọ fún ọ pé,

‘Ṣé ìwọ náà ti di aláìlágbára bíi tiwa ni?

Ṣé o ti dà bíi wa ni?

11 A ti mú ìyangàn rẹ lọ sínú Isà Òkú,*

Ìró àwọn ohun ìkọrin rẹ olókùn tín-ín-rín.+

Àwọn ìdin tẹ́ rẹrẹ lábẹ́ rẹ bí ibùsùn,

Kòkòrò mùkúlú sì ni ìbora rẹ.’

12 Wo bí o ṣe já bọ́ láti ọ̀run,

Ìwọ ẹni tó ń tàn, ọmọ òwúrọ̀!

Wo bí a ṣe gé ọ já bọ́ lulẹ̀,

Ìwọ tó ṣẹ́gun àwọn orílẹ̀-èdè!+

13 O sọ lọ́kàn rẹ pé, ‘Màá gòkè lọ sí ọ̀run.+

Màá gbé ìtẹ́ mi ga ju àwọn ìràwọ̀ Ọlọ́run,+

Màá sì jókòó sórí òkè ìpàdé,

Láwọn ibi tó jìnnà jù ní àríwá.+

14 Màá gòkè lọ sórí àwọsánmà;*

Màá mú ara mi jọ Ẹni Gíga Jù Lọ.’

15 Kàkà bẹ́ẹ̀, a máa sọ̀ ọ́ kalẹ̀ lọ sínú Isà Òkú,*

Sí àwọn ibi tó jìnnà jù nínú kòtò.

16 Àwọn tó rí ọ máa tẹjú mọ́ ọ;

Wọ́n máa yẹ̀ ọ́ wò fínnífínní, wọ́n á sọ pé,

‘Ṣé ọkùnrin tó ń mi ayé tìtì nìyí,

Tó kó jìnnìjìnnì bá àwọn ìjọba,+

17 Tó mú kí ilẹ̀ ayé tí à ń gbé dà bí aginjù,

Tó sì gba àwọn ìlú rẹ̀,+

Tí kò jẹ́ kí àwọn ẹlẹ́wọ̀n rẹ̀ pa dà sílé?’+

18 Gbogbo ọba àwọn orílẹ̀-èdè yòókù,

Àní, gbogbo wọn dùbúlẹ̀ nínú ògo,

Kálukú nínú ibojì* rẹ̀.

19 Àmọ́ a sọ ìwọ nù láìní sàréè,

Bí èéhù* tí a kórìíra,

Tí wọ́n fi àwọn tí a fi idà gún pa, bò bí aṣọ,

Tó sọ̀ kalẹ̀ lọ bá àwọn òkúta inú kòtò,

Bí òkú tí wọ́n fẹsẹ̀ tẹ̀ mọ́lẹ̀.

20 O ò ní lọ bá wọn nínú sàréè,

Torí o run ilẹ̀ rẹ,

O pa àwọn èèyàn tìrẹ.

A ò ní dárúkọ ọmọ àwọn aṣebi mọ́ títí láé.

21 Ẹ ṣètò ibi ìpẹran fún àwọn ọmọ rẹ̀,

Torí ẹ̀bi àwọn baba ńlá wọn,

Kí wọ́n má bàa dìde, kí wọ́n sì gba ayé,

Kí wọ́n wá fi àwọn ìlú wọn kún ilẹ̀ náà.”

22 “Màá dìde sí wọn,”+ ni Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun wí.

“Màá pa orúkọ àti àṣẹ́kù run, màá sì pa àtọmọdọ́mọ àti ìran tó ń bọ̀ run kúrò ní Bábílónì,”+ ni Jèhófà wí.

23 “Màá sọ ọ́ di ibùgbé àwọn òòrẹ̀ àti agbègbè tó ní irà, màá sì fi ìgbálẹ̀ ìparun gbá a,”+ ni Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun wí.

24 Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun ti búra pé:

“Bí mo ṣe gbèrò gẹ́lẹ́ ló máa rí,

Ohun tí mo sì pinnu gẹ́lẹ́ ló máa ṣẹ.

25 Màá fọ́ ará Ásíríà náà túútúú ní ilẹ̀ mi,

Màá sì tẹ̀ ẹ́ mọ́lẹ̀ lórí àwọn òkè mi.+

Àjàgà rẹ̀ máa kúrò lọ́rùn wọn,

Ẹrù rẹ̀ sì máa kúrò ní èjìká wọn.”+

26 Ohun tí a ti pinnu láti ṣe* sí gbogbo ayé nìyí,

Ọwọ́ tí a sì nà jáde sí* gbogbo orílẹ̀-èdè nìyí.

27 Torí pé Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun ti pinnu,

Ta ló lè dà á rú?+

Ó ti na ọwọ́ rẹ̀ jáde,

Ta ló sì lè dá a pa dà?+

28 Ní ọdún tí Ọba Áhásì kú,+ ìkéde yìí wáyé, pé:

29 “Kí ẹnì kankan nínú rẹ má yọ̀, ìwọ Filísíà,

Torí pé ọ̀pá ẹni tó ń lù ọ́ ti kán.

Torí ejò olóró+ máa jáde látinú gbòǹgbò ejò,+

Ọmọ rẹ̀ sì máa jẹ́ ejò oníná tó ń fò.*

30 Tí àkọ́bí àwọn ẹni rírẹlẹ̀ bá ń jẹun,

Tí àwọn aláìní sì dùbúlẹ̀ láìséwu,

Màá fi ìyàn pa gbòǹgbò rẹ,

A sì máa pa ohun tó bá ṣẹ́ kù lára rẹ.+

31 Pohùn réré ẹkún, ìwọ ẹnubodè! Ké jáde, ìwọ ìlú!

Ọkàn gbogbo yín máa domi, ẹ̀yin Filísíà!

Torí èéfín ń rú bọ̀ láti àríwá,

Kò sì sẹ́ni tí kì í ṣe kánkán nínú ọ̀wọ́ ọmọ ogun rẹ̀.”

32 Báwo ni kí wọ́n ṣe dá àwọn ìránṣẹ́ orílẹ̀-èdè náà lóhùn?

Pé Jèhófà ti fi ìpìlẹ̀ Síónì lélẹ̀+

Àti pé àwọn tó rẹlẹ̀ nínú àwọn èèyàn rẹ̀ máa fi ibẹ̀ ṣe ààbò.

15 Ọ̀rọ̀ ìkéde sí Móábù:+

Torí a ti pa á run ní òru kan,

A ti pa Árì+ ti Móábù lẹ́nu mọ́.

Torí a ti pa á run ní òru kan,

A ti pa Kírì+ ti Móábù lẹ́nu mọ́.

 2 Ó ti gòkè lọ sí Ilé* àti sí Díbónì,+

Lọ sí àwọn ibi gíga láti sunkún.

Móábù ń sunkún torí Nébò+ àti torí Médébà.+

Wọ́n fá gbogbo orí korodo,+ wọ́n gé gbogbo irùngbọ̀n mọ́lẹ̀.+

 3 Wọ́n wọ aṣọ ọ̀fọ̀* lójú ọ̀nà.

Gbogbo wọn ń pohùn réré ẹkún lórí àwọn òrùlé àtàwọn ojúde ìlú wọn;

Wọ́n ń sunkún bí wọ́n ṣe ń sọ̀ kalẹ̀ lọ.+

 4 Hẹ́ṣíbónì àti Éléálè+ ké jáde;

Wọ́n gbọ́ ohùn wọn ní Jáhásì+ lọ́hùn-ún lọ́hùn-ún.

Ìdí nìyẹn tí àwọn ọkùnrin Móábù tó dira ogun fi ń kígbe ṣáá.

Ó* ń gbọ̀n rìrì.

 5 Ọkàn mi ń ké jáde torí Móábù.

Àwọn tó sá níbẹ̀ ti sá lọ sí Sóárì+ àti Ẹgilati-ṣẹ́líṣíyà+ lọ́hùn-ún lọ́hùn-ún.

Wọ́n ń sunkún bí wọ́n ṣe ń gòkè lọ sí Lúhítì;

Wọ́n ń ké lójú ọ̀nà Hórónáímù torí àjálù náà.+

 6 Torí omi Nímúrímù ti gbẹ táútáú;

Koríko tútù ti gbẹ dà nù,

Kò sí koríko mọ́, kò sì sí ewéko tútù kankan mọ́.

 7 Ìdí nìyẹn tí wọ́n fi ń kó àwọn ohun tó ṣẹ́ kù ní ilé ìkẹ́rùsí wọn àti ọrọ̀ wọn;

Wọ́n ń sọdá àfonífojì àwọn igi pọ́pílà.

 8 Torí igbe wọn ń dún ní gbogbo ilẹ̀ Móábù.+

Ìpohùn réré ẹkún náà dé Égíláímù;

Ó lọ títí dé Bia-élímù.

 9 Torí ẹ̀jẹ̀ kún inú omi Dímónì,

Mo ṣì máa ṣe jù bẹ́ẹ̀ lọ fún Dímónì:

Kìnnìún máa pa àwọn tó yè bọ́ ní Móábù

Àti àwọn tó ṣẹ́ kù ní ilẹ̀ náà.+

16 Ẹ fi àgbò ránṣẹ́ sí alákòóso ilẹ̀ náà,

Láti Sẹ́ẹ́là gba aginjù

Lọ sórí òkè ọmọbìnrin Síónì.

 2 Bí ẹyẹ tí wọ́n lé kúrò nínú ìtẹ́ rẹ̀ +

Ni àwọn ọmọbìnrin Móábù máa rí níbi tó ṣeé fẹsẹ̀ gbà nínú odò Áánónì.+

 3 “Ẹ gbani nímọ̀ràn, ẹ tẹ̀ lé ìpinnu náà.

Jẹ́ kí òjìji rẹ ní ọ̀sán gangan dà bí òru.

Fi àwọn tí wọ́n fọ́n ká pa mọ́, má sì dalẹ̀ àwọn tó ń sá lọ.

 4 Kí àwọn èèyàn mi tó fọ́n ká máa gbé inú rẹ, ìwọ Móábù.

Di ibi ààbò fún wọn torí ẹni tó ń pani run.+

Òpin máa dé bá aninilára,

Ìparun náà máa dópin,

Àwọn tó ń tẹ ẹlòmíì mọ́lẹ̀ sì máa pa rẹ́ ní ayé.

 5 Ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ máa wá mú kí ìtẹ́ kan fìdí múlẹ̀ gbọn-in.

Ẹni tó jókòó sórí rẹ̀ nínú àgọ́ Dáfídì máa jẹ́ olóòótọ́;+

Ó máa dá ẹjọ́ bó ṣe tọ́, ó sì máa yára ṣe òdodo.”+

 6 A ti gbọ́ bí Móábù ṣe ń gbéra ga, ó ń gbéra ga gan-an;+

Bó ṣe ń gbéra ga, tó ń yangàn, tó sì ń bínú;+

Àmọ́ pàbó ni ọ̀rọ̀ asán rẹ̀ máa já sí.

 7 Torí náà, Móábù máa pohùn réré ẹkún torí Móábù;

Gbogbo wọn máa pohùn réré ẹkún.+

Àwọn tí wọ́n lù máa dárò torí ìṣù àjàrà gbígbẹ ti Kiri-hárésétì.+

 8 Torí àwọn ilẹ̀ onípele Hẹ́ṣíbónì+ ti gbẹ,

Àjàrà Síbúmà,+

Àwọn alákòóso àwọn orílẹ̀-èdè ti tẹ àwọn ẹ̀ka rẹ̀ tó pupa fòò* mọ́lẹ̀;

Wọ́n ti lọ títí dé Jásérì;+

Wọ́n ti tàn dé aginjù.

Àwọn ọ̀mùnú rẹ̀ ti tàn kálẹ̀, wọ́n sì ti lọ títí dé òkun.

 9 Ìdí nìyẹn tí màá fi sunkún torí àjàrà Síbúmà bí mo ṣe ń sunkún torí Jásérì.

Màá fi omijé mi rin ọ́ gbingbin, ìwọ Hẹ́ṣíbónì àti Éléálè,+

Torí pé igbe tí wọ́n ń ké torí èso ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn rẹ àti ìkórè rẹ ti dópin.*

10 A ti mú ayọ̀ àti ìdùnnú kúrò nínú ọgbà eléso,

Kò sì sí orin ayọ̀ tàbí ariwo nínú àwọn ọgbà àjàrà.+

Ẹni tó ń fẹsẹ̀ tẹ àjàrà kò tẹ̀ ẹ́ mọ́ ní àwọn ibi ìfúntí láti ṣe wáìnì,

Torí mo ti mú kí ariwo náà dáwọ́ dúró.+

11 Ìdí nìyẹn tó fi jẹ́ pé inú mi lọ́hùn-ún ń ru sókè torí Móábù,+

Bí ìgbà tí wọ́n ń ta háàpù,

Àti inú mi lọ́hùn-ún torí Kiri-hárésétì.+

12 Kódà, tí Móábù bá tán ara rẹ̀ lókun lórí ibi gíga, tó sì lọ gbàdúrà nínú ibi mímọ́ rẹ̀, kò ní rí nǹkan kan ṣe.+

13 Ọ̀rọ̀ tí Jèhófà ti sọ nípa Móábù nìyí. 14 Ní báyìí, Jèhófà sọ pé: “Láàárín ọdún mẹ́ta, bí iye ọdún alágbàṣe,* onírúurú rúkèrúdò ni wọ́n máa fi dójú ti ògo Móábù, àwọn tó máa ṣẹ́ kù máa kéré gan-an, wọn ò sì ní já mọ́ nǹkan kan.”+

17 Ọ̀rọ̀ ìkéde sí Damásíkù:+

“Wò ó! Damásíkù ò ní jẹ́ ìlú mọ́,

Ó sì máa di àwókù.+

 2 A máa pa àwọn ìlú Áróérì tì; +

Wọ́n máa di ibi tí àwọn agbo ẹran ń dùbúlẹ̀ sí

Ẹnì kankan ò sì ní dẹ́rù bà wọ́n.

 3 Àwọn ìlú olódi ò ní sí mọ́ ní Éfúrémù,+

Ìjọba ò sì ní sí mọ́ ní Damásíkù;+

Àwọn tó ṣẹ́ kù lára Síríà

Sì máa dà bí ògo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì,”* ni Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun wí.

 4 “Ní ọjọ́ yẹn, ògo Jékọ́bù máa dín kù,

Ara rẹ̀ tó dá ṣáṣá* sì máa joro.

 5 Ó máa dà bí ìgbà tí ẹni tó ń kórè bá ń kó ọkà tó wà ní ìdúró jọ,

Tí apá rẹ̀ sì ń kórè ṣírí ọkà,

Bí ìgbà tí èèyàn ń pèéṣẹ́* ọkà ní Àfonífojì* Réfáímù.+

 6 Èéṣẹ́ nìkan ló máa ṣẹ́ kù,

Bí ìgbà tí wọ́n lu igi ólífì:

Ólífì méjì tàbí mẹ́ta tó pọ́n nìkan ló ṣẹ́ kù lórí ẹ̀ka tó ga jù,

Mẹ́rin tàbí márùn-ún nìkan lórí àwọn ẹ̀ka rẹ̀ tó ń so èso,”+ ni Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì wí.

7 Ní ọjọ́ yẹn, èèyàn máa yíjú sókè wo Aṣẹ̀dá rẹ̀, ojú rẹ̀ á sì máa wo Ẹni Mímọ́ Ísírẹ́lì. 8 Kò ní wo àwọn pẹpẹ,+ iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀;+ kò sì ní tẹjú mọ́ ohun tó fi ìka rẹ̀ ṣe, ì báà jẹ́ àwọn òpó òrìṣà* tàbí àwọn pẹpẹ tùràrí.

 9 Ní ọjọ́ yẹn, àwọn ìlú ààbò rẹ̀ máa dà bí ibi tí wọ́n pa tì lórí ilẹ̀ tí igi pọ̀ sí,+

Bí ẹ̀ka tí wọ́n pa tì níwájú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì;

Ó máa di ahoro.

10 Torí o ti gbàgbé Ọlọ́run+ ìgbàlà rẹ;

O ò rántí Àpáta+ ààbò rẹ.

Ìdí nìyẹn tí o fi gbin àwọn ohun tó rẹwà,*

Tí o sì fi ọ̀mùnú àjèjì* gbìn ín.

11 Ní ọ̀sán, o rọra ṣe ọgbà yí oko rẹ ká,

Ní àárọ̀, o mú kí irúgbìn rẹ rú jáde,

Àmọ́ ìkórè ò ní sí ní ọjọ́ àìsàn àti ìrora tí kò ṣeé wò sàn.+

12 Fetí sílẹ̀! Ọ̀pọ̀ èèyàn ń fa rúkèrúdò,

Wọ́n ń pariwo bí omi òkun tó ń ru gùdù!

Àwọn orílẹ̀-èdè ń hó yèè,

Ìró wọn dà bí ariwo alagbalúgbú omi!

13 Ìró àwọn orílẹ̀-èdè máa dà bí ariwo omi púpọ̀.

Ó máa bá wọn wí, wọ́n sì máa sá lọ jìnnà réré,

Wọ́n á sá lọ bí ìgbà tí atẹ́gùn ń fẹ́ ìyàngbò* lórí àwọn òkè,

Bí ẹ̀gún* tí ìjì ń gbé yípo yípo.

14 Ìbẹ̀rù wà ní ìrọ̀lẹ́.

Kó tó di àárọ̀, wọn ò sí mọ́.

Ìpín àwọn tó ń kó wa lẹ́rù nìyí,

Ohun tó sì máa ṣẹlẹ̀ sí àwọn tó ń kó ohun ìní wa nìyí.

18 Ilẹ̀ tí ìyẹ́ àwọn kòkòrò ti ń kùn yùnmù gbé,

Ní agbègbè àwọn odò Etiópíà!+

 2 Ó ń rán àwọn aṣojú gba ojú òkun,

Wọ́n gba orí omi nínú àwọn ọkọ̀ tí wọ́n fi òrépèté ṣe, ó ní:

“Ẹ lọ, ẹ̀yin ìránṣẹ́ tó yára kánkán,

Sí orílẹ̀-èdè tó ga, tí ara rẹ̀ sì ń dán,*

Sí àwọn èèyàn tí wọ́n ń bẹ̀rù níbi gbogbo,+

Sí orílẹ̀-èdè tó lágbára, tó máa ń ṣẹ́gun,*

Tí àwọn odò ti wọ́ ilẹ̀ rẹ̀ lọ.”

 3 Gbogbo ẹ̀yin tí ẹ̀ ń gbé ilẹ̀ náà àti ẹ̀yin tí ẹ̀ ń gbé ayé,

Ohun tí ẹ máa rí máa dà bí àmì* tí wọ́n gbé sókè lórí àwọn òkè,

Ẹ sì máa gbọ́ ìró tó dà bí ìgbà tí wọ́n ń fun ìwo.

 4 Torí ohun tí Jèhófà sọ fún mi nìyí:

“Màá wà láìsí ẹni tó máa yọ mí lẹ́nu, màá sì máa wo* ibi tí mo fìdí múlẹ̀ sí,

Bí ooru tó rọra ń mú nínú ìtànṣán oòrùn,

Bí ìrì tó ń sẹ̀ látinú ìkùukùu* nínú ooru ìgbà ìkórè.

 5 Torí kó tó di ìgbà ìkórè,

Tí ìtànná bá yọ tán, tí ìtànná òdòdó sì ti di èso àjàrà tó pọ́n,

Wọ́n máa fi ohun ìrẹ́wọ́ ọ̀gbìn gé àwọn ọ̀mùnú rẹ̀ kúrò,

Wọ́n máa gé àwọn ọwọ́ rẹ̀ kúrò, wọ́n á sì kó o dà nù.

 6 Wọ́n á fi gbogbo rẹ̀ sílẹ̀ fún àwọn ẹyẹ aṣọdẹ lórí òkè

Àti àwọn ẹranko orí ilẹ̀.

Orí wọn ni àwọn ẹyẹ aṣọdẹ ti máa lo ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn,

Gbogbo ẹranko orí ilẹ̀ sì máa lo ìgbà ìkórè lórí wọn.

 7 Ní àkókò yẹn, wọ́n máa mú ẹ̀bùn wá fún Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun,

Látọ̀dọ̀ orílẹ̀-èdè tó ga, tí ara rẹ̀ sì ń dán,*

Látọ̀dọ̀ àwọn èèyàn tí wọ́n ń bẹ̀rù níbi gbogbo,

Látọ̀dọ̀ orílẹ̀-èdè tó lágbára, tó máa ń ṣẹ́gun,*

Tí àwọn odò ti wọ́ ilẹ̀ rẹ̀ lọ

Sí ibi tó ń jẹ́ orúkọ Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun, Òkè Síónì.”+

19 Ọ̀rọ̀ ìkéde sí Íjíbítì:+

Wò ó! Jèhófà gun àwọsánmà tó ń yára kánkán, ó sì ń bọ̀ wá sí Íjíbítì.

Àwọn ọlọ́run Íjíbítì tí kò ní láárí máa gbọ̀n rìrì níwájú rẹ̀,+

Ọkàn Íjíbítì sì máa domi nínú rẹ̀.

 2 “Màá mú kí àwọn ọmọ Íjíbítì dojú kọ ara wọn,

Wọ́n á sì bá ara wọn jà,

Kálukú máa bá arákùnrin rẹ̀ àti ọmọnìkejì rẹ̀ jà,

Ìlú máa bá ìlú jà, ìjọba sì máa bá ìjọba jà.

 3 Ìdààmú sì máa bá Íjíbítì láàárín rẹ̀,

Màá sì da àwọn ohun tó ń gbèrò rú.+

Wọ́n máa yíjú sí àwọn ọlọ́run tí kò ní láárí,

Àwọn atujú, àwọn abẹ́mìílò àti àwọn woṣẹ́woṣẹ́.+

 4 Màá fa Íjíbítì lé ọ̀gá tó le lọ́wọ́,

Ọba tó sì burú máa jẹ lé wọn lórí,”+ ni Olúwa tòótọ́, Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun wí.

 5 Omi òkun máa gbẹ,

Kò ní sí omi nínú odò, ó sì máa gbẹ táútáú.+

 6 Àwọn odò á máa rùn;

Àwọn ipa odò Náílì nílẹ̀ Íjíbítì máa fà, ó sì máa gbẹ táútáú.

Àwọn esùsú* àti koríko etídò máa jẹrà.+

 7 Àwọn ewéko tó wà létí odò Náílì, ní bèbè Náílì,

Àti gbogbo ilẹ̀ tí wọ́n fúnrúgbìn sí létí odò Náílì+ máa gbẹ.+

Ó máa fẹ́ lọ, kò sì ní sí mọ́.

 8 Àwọn apẹja máa ṣọ̀fọ̀,

Àwọn tó ń ju ìwọ̀ ẹja sínú odò Náílì máa dárò,

Àwọn tó sì ń na àwọ̀n ìpẹja wọn sí ojú omi máa dín kù.

 9 Ojú máa ti àwọn tó ń ya ọ̀gbọ̀+

Àti àwọn tó ń hun aṣọ funfun.

10 Wọ́n máa tẹ àwọn ahunṣọ rẹ̀ rẹ́;

Gbogbo alágbàṣe rẹ̀ máa kẹ́dùn.*

11 Òmùgọ̀ ni àwọn olórí Sóánì.+

Ìmọ̀ràn tí kò bọ́gbọ́n mu làwọn tó gbọ́n jù nínú àwọn agbani-nímọ̀ràn Fáráò ń mú wá.+

Báwo lẹ ṣe máa sọ fún Fáráò pé:

“Àtọmọdọ́mọ àwọn ọlọ́gbọ́n ni mí,

Àtọmọdọ́mọ àwọn ọba àtijọ́”?

12 Àwọn ọlọ́gbọ́n rẹ wá dà?+

Jẹ́ kí wọ́n sọ fún ọ, tí wọ́n bá mọ ohun tí Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun ti pinnu nípa Íjíbítì.

13 Àwọn olórí Sóánì ti hùwà òpònú;

Wọ́n ti tan àwọn olórí Nófì*+ jẹ;

Àwọn ìjòyè àwọn ẹ̀ya rẹ̀ ti kó Íjíbítì ṣìnà.

14 Jèhófà ti fi ẹ̀mí ìdàrúdàpọ̀ kọ lù ú;+

Wọ́n sì ti kó Íjíbítì ṣìnà nínú gbogbo ohun tó ń ṣe,

Bí ọ̀mùtí tó ń ta gọ̀ọ́gọ̀ọ́ nínú èébì rẹ̀.

15 Íjíbítì ò sì ní rí iṣẹ́ kankan ṣe,

Ì báà jẹ́ orí tàbí ìrù, ọ̀mùnú tàbí koríko etídò.*

16 Ní ọjọ́ yẹn, Íjíbítì máa dà bí obìnrin, ó máa gbọ̀n rìrì, ẹ̀rù á sì máa bà á torí ọwọ́ ìhàlẹ̀ tí Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun gbé sókè sí i.+ 17 Ilẹ̀ Júdà sì máa di ohun ìbẹ̀rù fún Íjíbítì. Tí wọ́n bá gbọ́ orúkọ rẹ̀, ẹ̀rù máa bà wọ́n torí ìpinnu tí Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun ti ṣe lòdì sí wọn.+

18 Ní ọjọ́ yẹn, ìlú márùn-ún máa wà nílẹ̀ Íjíbítì tí wọ́n ń sọ èdè Kénáánì,+ tí wọ́n á sì búra pé àwọn máa dúró ti Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun. Ìlú kan á máa jẹ́ Ìlú Ìyalulẹ̀.

19 Ní ọjọ́ yẹn, pẹpẹ kan máa wà fún Jèhófà ní àárín ilẹ̀ Íjíbítì, òpó kan sì máa wà fún Jèhófà níbi ààlà rẹ̀. 20 Ó máa jẹ́ àmì àti ẹ̀rí sí Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun nílẹ̀ Íjíbítì; torí wọ́n máa ké pe Jèhófà nítorí àwọn aninilára, ó sì máa rán olùgbàlà kan sí wọn, ẹni tó tóbi lọ́lá, tó máa gbà wọ́n là. 21 Jèhófà máa jẹ́ kí àwọn ọmọ Íjíbítì mọ òun, àwọn ọmọ Íjíbítì sì máa mọ Jèhófà ní ọjọ́ yẹn, wọ́n máa rúbọ, wọ́n á mú ẹ̀bùn wá, wọ́n á jẹ́jẹ̀ẹ́ fún Jèhófà, wọ́n á sì san án. 22 Jèhófà máa kọ lu Íjíbítì,+ á kọ lù ú, á sì wò ó sàn; wọ́n á pa dà sọ́dọ̀ Jèhófà, á gbọ́ ẹ̀bẹ̀ wọn, á sì wò wọ́n sàn.

23 Ní ọjọ́ yẹn, ọ̀nà kan máa jáde+ láti Íjíbítì lọ sí Ásíríà. Ásíríà máa wá sí Íjíbítì, Íjíbítì sì máa lọ sí Ásíríà, Íjíbítì àti Ásíríà sì jọ máa sin Ọlọ́run. 24 Ní ọjọ́ yẹn, Ísírẹ́lì máa ṣe ìkẹta Íjíbítì àti Ásíríà,+ àwọn tí a bù kún ní àárín ayé, 25 torí Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun ti máa súre fún un pé: “Ìbùkún ni fún àwọn èèyàn mi, Íjíbítì, àti iṣẹ́ ọwọ́ mi, Ásíríà, àti ogún mi, Ísírẹ́lì.”+

20 Ní ọdún tí Ságónì ọba Ásíríà rán Tátánì* lọ sí Áṣídódì,+ ó bá Áṣídódì jagun, ó sì gbà á.+ 2 Ní àkókò yẹn, Jèhófà gbẹnu Àìsáyà+ ọmọ Émọ́ọ̀sì sọ̀rọ̀, ó ní: “Lọ, kí o tú aṣọ ọ̀fọ̀* kúrò ní ìbàdí rẹ, kí o sì bọ́ bàtà kúrò ní ẹsẹ̀ rẹ.” Ó sì ṣe bẹ́ẹ̀, ó wá ń rìn káàkiri ní ìhòòhò* àti láìwọ bàtà.

3 Jèhófà wá sọ pé: “Bí ìránṣẹ́ mi Àìsáyà ṣe rìn káàkiri ní ìhòòhò, láìwọ bàtà fún ọdún mẹ́ta, láti fi ṣe àmì+ àti àpẹẹrẹ ohun tó máa ṣẹlẹ̀ sí Íjíbítì+ àti Etiópíà,+ 4 bẹ́ẹ̀ gẹ́lẹ́ ni ọba Ásíríà máa kó àwọn ẹrú Íjíbítì+ àti Etiópíà lọ sí ìgbèkùn, àwọn ọmọdékùnrin àtàwọn àgbà ọkùnrin, ní ìhòòhò àti láìwọ bàtà, ìdí wọn á sì hàn síta, Íjíbítì máa rin ìhòòhò.* 5 Ẹ̀rù máa bà wọ́n, ojú sì máa tì wọ́n torí Etiópíà tí wọ́n gbẹ́kẹ̀ lé àti Íjíbítì tí wọ́n fi ń yangàn.* 6 Ní ọjọ́ yẹn, àwọn tó ń gbé ilẹ̀ etíkun yìí máa sọ pé, ‘Ẹ wo ohun tó ṣẹlẹ̀ sí ẹni tí a gbẹ́kẹ̀ lé, tí a sá lọ bá pé kó ràn wá lọ́wọ́, kó sì gbà wá lọ́wọ́ ọba Ásíríà! Báwo la ṣe máa yè bọ́ báyìí?’”

21 Ọ̀rọ̀ ìkéde sí aginjù òkun:*+

Ó ń bọ̀ bí ìjì tó fẹ́ kọjá ní gúúsù,

Láti aginjù, láti ilẹ̀ tó ń dẹ́rù bani.+

 2 A ti sọ ìran kan tó le fún mi:

Ọ̀dàlẹ̀ ń dalẹ̀,

Apanirun sì ń pani run.

Gòkè lọ, ìwọ Élámù! Gbógun tini, ìwọ Mídíà!+

Màá fòpin sí gbogbo ẹ̀dùn ọkàn tó mú kó bá àwọn èèyàn.+

 3 Ìdí nìyẹn tí mo fi ń jẹ̀rora gidigidi.*+

Àwọn iṣan mi ń sún kì,

Bíi ti obìnrin tó ń bímọ.

Ìdààmú tó bá mi ò jẹ́ kí n gbọ́ràn;

Ìyọlẹ́nu tó bá mi ò jẹ́ kí n ríran.

 4 Ọkàn mi dà rú; jìnnìjìnnì bò mí.

Ìrọ̀lẹ́ tí mò ń retí ń dẹ́rù bà mí.

 5 Ẹ tẹ́ tábìlì, kí ẹ sì to àwọn ìjókòó!

Ẹ jẹ, kí ẹ sì mu!+

Ẹ dìde, ẹ̀yin ìjòyè, ẹ fi òróró yan* apata!

 6 Torí ohun tí Jèhófà sọ fún mi nìyí:

“Lọ, yan aṣọ́nà, kí o sì ní kó ròyìn ohun tó bá rí.”

 7 Ó sì rí kẹ̀kẹ́ ogun àtàwọn ẹṣin,

Kẹ̀kẹ́ ogun kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́,

Kẹ̀kẹ́ ogun ràkúnmí.

Ó fara balẹ̀ wò ó, ó sì kíyè sí i dáadáa.

 8 Ó wá ké jáde bíi kìnnìún, ó ní:

“Jèhófà, orí ilé ìṣọ́ ni mò ń dúró sí nígbà gbogbo ní ọ̀sán,

Mi ò sì kúrò níbi tí a fi mí ṣọ́ ní gbogbo òru.+

 9 Wo ohun tó ń bọ̀:

Àwọn ọkùnrin wà nínú kẹ̀kẹ́ ogun tí wọ́n so àwọn ẹṣin mọ́!”+

Ó wá sọ pé:

“Ó ti ṣubú! Bábílónì ti ṣubú!+

Gbogbo ère gbígbẹ́ àwọn ọlọ́run rẹ̀ ló ti fọ́ sílẹ̀ túútúú!”+

10 Ẹ̀yin èèyàn mi tí wọ́n ti pa bí ọkà,

Ohun tó tinú ibi ìpakà mi jáde,*+

Mo ti sọ ohun tí mo gbọ́ fún ọ látọ̀dọ̀ Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun, Ọlọ́run Ísírẹ́lì.

11 Ọ̀rọ̀ ìkéde sí Dúmà:*

Ẹnì kan ń ké pè mí láti Séírì+ pé:

“Olùṣọ́, báwo ni òru ṣe rí?

Olùṣọ́, báwo ni òru ṣe rí?”

12 Olùṣọ́ sọ pé:

“Òwúrọ̀ ń bọ̀, bẹ́ẹ̀ náà ni òru.

Tí ẹ bá fẹ́ wádìí, ẹ wádìí.

Ẹ tún pa dà wá!”

13 Ọ̀rọ̀ ìkéde sí aṣálẹ̀ tó tẹ́jú:

Inú igbó, nínú aṣálẹ̀ tó tẹ́jú lẹ máa sùn mọ́jú,

Ẹ̀yin ará Dédánì+ tó ń rìnrìn àjò.

14 Ẹ gbé omi wá pàdé ẹni tí òùngbẹ ń gbẹ,

Ẹ̀yin tí ẹ̀ ń gbé ilẹ̀ Témà,+

Kí ẹ sì gbé oúnjẹ wá fún ẹni tó ń sá lọ.

15 Torí wọ́n ti sá fún àwọn idà, idà tí wọ́n fà yọ,

Fún ọrun tí wọ́n fà àti ogun tó gbóná janjan.

16 Torí ohun tí Jèhófà sọ fún mi nìyí: “Láàárín ọdún kan, bíi ti ọdún alágbàṣe,* gbogbo ògo Kídárì+ máa wá sí òpin. 17 Àwọn tó bá ṣẹ́ kù nínú àwọn jagunjagun Kídárì tí wọ́n ń ta ọfà máa kéré, torí Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì ti sọ ọ́.”

22 Ìkéde nípa Àfonífojì Ìran:*+

Kí ló ṣe yín, tí gbogbo yín fi lọ sórí àwọn òrùlé?

 2 Ìwọ tí rúkèrúdò kún inú rẹ,

Ìwọ ìlú aláriwo, ìlú tó ń yọ̀ gidigidi.

Kì í ṣe idà ni wọ́n fi pa àwọn èèyàn rẹ tí wọ́n pa,

Bẹ́ẹ̀ ni wọn ò kú sójú ogun.+

 3 Gbogbo àwọn apàṣẹwàá rẹ ti jọ sá lọ.+

Wọ́n mú wọn ní ẹlẹ́wọ̀n láìlo ọfà.

Gbogbo àwọn tí wọ́n rí ni wọ́n mú ní ẹlẹ́wọ̀n,+

Bí wọ́n tiẹ̀ sá lọ sí ọ̀nà jíjìn.

 4 Ìdí nìyẹn tí mo fi sọ pé: “Ẹ yí ojú yín kúrò lọ́dọ̀ mi,

Màá sì sunkún gidigidi.+

Ẹ má fi dandan sọ pé ẹ fẹ́ tù mí nínú

Torí ìparun ọmọbìnrin* àwọn èèyàn mi.+

 5 Torí ọjọ́ ìdàrúdàpọ̀, ìṣẹ́gun àti ìbẹ̀rù ni,+

Látọ̀dọ̀ Olúwa Ọba Aláṣẹ, Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun,

Ní Àfonífojì Ìran.

Wọ́n máa wó ògiri palẹ̀,+

Wọ́n sì máa kígbe sí òkè.

 6 Élámù+ gbé apó,

Pẹ̀lú àwọn tó ń gun kẹ̀kẹ́ ogun àtàwọn ẹṣin,*

Kírì+ sì ṣí* apata.

 7 Àwọn àfonífojì* rẹ tó dáa jù

Máa kún fún kẹ̀kẹ́ ogun,

Àwọn ẹṣin* sì máa dúró sí àyè wọn ní ẹnubodè,

 8 Wọ́n á mú aṣọ tí wọ́n ta bo* Júdà kúrò.

“Ní ọjọ́ yẹn, o máa wo apá ibi tí wọ́n ń kó nǹkan ìjà sí ní Ilé Igbó,+ 9 ẹ sì máa rí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àlàfo Ìlú Dáfídì.+ Ẹ máa gbá adágún omi ìsàlẹ̀ jọ.+ 10 Ẹ máa ka àwọn ilé Jerúsálẹ́mù, ẹ sì máa wó àwọn ilé náà láti fi mú kí ògiri náà túbọ̀ lágbára. 11 Láàárín ògiri méjèèjì, ẹ máa ṣe ohun tó lè gba adágún omi àtijọ́ dúró, àmọ́ ẹ ò ní wo Aṣẹ̀dá rẹ̀ Atóbilọ́lá, ẹ ò sì ní rí Ẹni tó dá a tipẹ́tipẹ́.

12 Ní ọjọ́ yẹn, Olúwa Ọba Aláṣẹ, Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun,

Máa ní kí wọ́n sunkún, kí wọ́n sì ṣọ̀fọ̀,+

Ó máa ní kí wọ́n fá orí, kí wọ́n sì wọ aṣọ ọ̀fọ̀.*

13 Àmọ́ dípò ìyẹn, wọ́n ń yọ̀, inú wọn sì ń dùn,

Wọ́n ń pa màlúù, wọ́n sì ń dúńbú àgùntàn,

Wọ́n ń jẹ ẹran, wọ́n sì ń mu wáìnì.+

‘Ẹ jẹ́ ká máa jẹ, ká sì máa mu, torí ọ̀la la máa kú.’”+

14 Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun wá ṣí ara rẹ̀ payá ní etí mi pé: “‘A ò ní ṣètùtù ẹ̀ṣẹ̀ yìí fún yín títí ẹ̀yin èèyàn yìí fi máa kú,’+ ni Olúwa Ọba Aláṣẹ, Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun wí.”

15 Ohun tí Olúwa Ọba Aláṣẹ, Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun, sọ nìyí: “Wọlé lọ bá ìríjú yìí, ìyẹn Ṣébínà,+ ẹni tó ń bójú tó ilé,* kí o sì sọ fún un pé, 16 ‘Kí ló jẹ́ tìrẹ níbí, ta sì ni èèyàn rẹ níbí, tí o fi gbẹ́ ibi ìsìnkú síbí fún ara rẹ?’ Ibi gíga ló ń gbẹ́ ibi ìsìnkú rẹ̀ sí; inú àpáta ló ń gbẹ́ ibi ìsinmi* sí fún ara rẹ̀. 17 ‘Wò ó! Jèhófà máa fi ọ́ sọ̀kò sílẹ̀, ìwọ ọkùnrin, ó sì máa fipá gbá ọ mú. 18 Ó dájú pé ó máa dì ọ́ le dan-in dan-in, ó sì máa jù ọ́ dà nù bíi bọ́ọ̀lù sí ilẹ̀ tó fẹ̀. Ibẹ̀ lo máa kú sí, ibẹ̀ sì ni àwọn kẹ̀kẹ́ ẹṣin rẹ ológo máa wà, èyí máa dójú ti ilé ọ̀gá rẹ. 19 Mo máa yọ ọ́ nípò, màá sì lé ọ kúrò ní ipò rẹ.

20 “‘Ní ọjọ́ yẹn, màá pe ìránṣẹ́ mi, Élíákímù+ ọmọ Hilikáyà, 21 màá wọ aṣọ rẹ fún un, màá de ọ̀já rẹ mọ́ ọn pinpin,+ màá sì gbé àṣẹ* rẹ lé e lọ́wọ́. Ó máa di bàbá àwọn tó ń gbé Jerúsálẹ́mù àti ilé Júdà. 22 Màá sì fi kọ́kọ́rọ́ ilé Dáfídì+ sí èjìká rẹ̀. Tó bá ṣí ibì kan, ẹnì kankan ò ní tì í; tó bá sì ti ibì kan, ẹnì kankan ò ní ṣí i. 23 Màá kàn án mọ́lẹ̀ bí èèkàn sí ibi tó máa wà títí lọ, ó sì máa dà bí ìtẹ́ ògo fún ilé bàbá rẹ̀. 24 Wọ́n máa gbé gbogbo ògo* ilé bàbá rẹ̀ kọ́ sára rẹ̀, àwọn àtọmọdọ́mọ àtàwọn ọmọ,* gbogbo ohun èlò kéékèèké, àwọn ohun èlò tó rí bí abọ́, títí kan gbogbo ìṣà ńlá.

25 “‘Ní ọjọ́ yẹn,’ ni Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun wí, ‘a máa yọ èèkàn tí a kàn mọ́ ibi tó máa wà títí lọ,+ a máa gé e lulẹ̀, ó sì máa ṣubú, ẹrù tó gbé máa ṣubú, ó sì máa pa run, torí Jèhófà fúnra rẹ̀ ti sọ ọ́.’”

23 Ìkéde nípa Tírè:+

Ẹ pohùn réré ẹkún, ẹ̀yin ọkọ̀ òkun Táṣíṣì!+

Torí a ti run èbúté; kò ṣeé wọ̀.

A ti ṣi í payá fún wọn láti ilẹ̀ Kítímù.+

 2 Ẹ dákẹ́ jẹ́ẹ́, ẹ̀yin tí ẹ̀ ń gbé ilẹ̀ etíkun.

Àwọn oníṣòwò láti Sídónì,+ tó ń sọdá òkun ti kún inú rẹ.

 3 Ọkà* Ṣíhórì*+ gba orí omi púpọ̀,

Ìkórè Náílì, owó tó ń wọlé fún un,

Tó ń mú èrè wá fún àwọn orílẹ̀-èdè.+

 4 Kí ojú tì ọ́, ìwọ Sídónì, ìwọ ibi ààbò òkun,

Torí òkun ti sọ pé:

“Mi ò ní ìrora ìrọbí, mi ò sì tíì bímọ,

Bẹ́ẹ̀ ni mi ò tọ́ àwọn ọ̀dọ́kùnrin tàbí ọ̀dọ́bìnrin* dàgbà.”+

 5 Bí ìgbà tí wọ́n gbọ́ ìròyìn nípa Íjíbítì,+

Àwọn èèyàn máa jẹ̀rora torí ìròyìn tí wọ́n gbọ́ nípa Tírè.+

 6 Ẹ sọdá sí Táṣíṣì!

Ẹ pohùn réré ẹkún, ẹ̀yin tí ẹ̀ ń gbé ilẹ̀ etíkun!

 7 Ṣé ìlú yín tó ń yọ̀ látọjọ́ tó ti pẹ́ nìyí, láti ìgbà àtijọ́ rẹ̀?

Ẹsẹ̀ rẹ̀ máa ń gbé e lọ sí àwọn ilẹ̀ tó jìn kó lè gbé ibẹ̀.

 8 Ta ló pinnu èyí sí Tírè,

Ẹni tó ń déni ládé,

Tí àwọn oníṣòwò rẹ̀ jẹ́ ìjòyè,

Tí wọ́n ń bọlá fún àwọn ọlọ́jà rẹ̀ ní gbogbo ayé?+

 9 Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun fúnra rẹ̀ ti pinnu èyí,

Láti tẹ́ńbẹ́lú bó ṣe ń fi gbogbo ẹwà rẹ̀ yangàn,

Láti rẹ gbogbo àwọn tí wọ́n ń bọlá fún ní ayé sílẹ̀.+

10 Sọdá ilẹ̀ rẹ bí odò Náílì, ìwọ ọmọbìnrin Táṣíṣì.

Kò sí ibi tí wọ́n ti ń ṣe ọkọ̀ òkun* mọ́.+

11 Ó ti na ọwọ́ rẹ̀ sórí òkun;

Ó ti mi àwọn ìjọba jìgìjìgì.

Jèhófà ti pàṣẹ pé kí wọ́n pa àwọn ibi ààbò Foníṣíà run.+

12 Ó sì sọ pé: “O ò ní yọ̀ mọ́,+

Ìwọ ẹni tí wọ́n ń fìyà jẹ, ọmọbìnrin Sídónì tó jẹ́ wúńdíá.

Dìde, sọdá sí Kítímù.+

O ò ní ní ìsinmi níbẹ̀ pàápàá.”

13 Wò ó! Ilẹ̀ àwọn ará Kálídíà.+

Àwọn èèyàn náà nìyí, kì í ṣe Ásíríà,+

Wọ́n sọ ọ́ di ibi tí àwọn tó ń lọ sínú aṣálẹ̀ máa ń lọ.

Wọ́n ti kọ́ àwọn ilé gogoro láti dó tì í;

Wọ́n ti ya àwọn ilé gogoro rẹ̀ lulẹ̀,+

Wọ́n ti sọ ọ́ di ibi tó rún wómúwómú.

14 Ẹ pohùn réré ẹkún, ẹ̀yin ọkọ̀ òkun Táṣíṣì,

Torí ibi ààbò yín ti pa run.+

15 Ní ọjọ́ yẹn, wọ́n máa gbàgbé Tírè fún àádọ́rin (70) ọdún,+ bí ayé ìgbà* ọba kan. Lópin àádọ́rin (70) ọdún, ó máa ṣẹlẹ̀ sí Tírè bí orin aṣẹ́wó kan tó sọ pé:

16 “Mú háàpù, lọ yí ká ìlú, ìwọ aṣẹ́wó tí wọ́n ti gbàgbé.

Ta háàpù rẹ dáadáa;

Kọ orin tó pọ̀,

Kí wọ́n lè rántí rẹ.”

17 Ní òpin àádọ́rin (70) ọdún, Jèhófà máa rántí Tírè, ó máa pa dà sídìí ọrọ̀ rẹ̀, á sì máa bá gbogbo ìjọba ayé tó wà lórí ilẹ̀ ayé ṣe ìṣekúṣe. 18 Àmọ́ èrè rẹ̀ àti ọrọ̀ rẹ̀ máa di ohun mímọ́ fún Jèhófà. Kò ní kó o pa mọ́ tàbí kó tò ó jọ, torí pé ọrọ̀ rẹ̀ máa di ti àwọn tó ń gbé iwájú Jèhófà, kí wọ́n lè jẹun ní àjẹyó, kí wọ́n sì wọ aṣọ aláràbarà.+

24 Wò ó! Jèhófà máa sọ ilẹ̀ náà* di òfìfo, ó sì máa sọ ọ́ di ahoro.+

Ó ń dojú rẹ̀ dé,*+ ó sì ń tú àwọn tó ń gbé inú rẹ̀ ká.+

 2 Bákan náà ló máa rí fún gbogbo èèyàn:

Àwọn èèyàn àti àlùfáà,

Ìránṣẹ́kùnrin àti ọ̀gá rẹ̀ ọkùnrin,

Ìránṣẹ́bìnrin àti ọ̀gá rẹ̀ obìnrin,

Ẹni tó ń rà àti ẹni tó ń tà,

Ẹni tó ń yáni ní nǹkan àti ẹni tó ń yá nǹkan,

Ẹni tó ń yáni lówó àti ẹni tó ń yáwó.+

 3 Wọ́n máa mú kí ilẹ̀ náà ṣófo pátápátá;

Wọ́n máa kó gbogbo ẹrù rẹ̀,+

Torí Jèhófà ti sọ ọ̀rọ̀ yìí.

 4 Ilẹ̀ náà ń ṣọ̀fọ̀;*+ ó ń joro.

Ilẹ̀ tó ń méso jáde ò lọ́ràá mọ́; ó ti ń ṣá.

Àwọn gbajúmọ̀ ilẹ̀ náà ti rẹ̀ dà nù.

 5 Àwọn tó ń gbé ilẹ̀ náà ti ba ibẹ̀ jẹ́,+

Torí wọ́n ti rú òfin,+

Wọ́n ti yí ìlànà pa dà,+

Wọ́n sì da májẹ̀mú tó wà pẹ́ títí.*+

 6 Ìdí nìyẹn tí ègún fi jẹ ilẹ̀ náà run,+

Tí a sì dẹ́bi fún àwọn tó ń gbé ibẹ̀.

Ìdí nìyẹn tí àwọn tó ń gbé ilẹ̀ náà fi dín kù,

Àwọn tó sì ṣẹ́ kù níbẹ̀ ò pọ̀ rárá.+

 7 Wáìnì tuntun ń ṣọ̀fọ̀,* àjàrà rọ,+

Gbogbo àwọn tí inú wọn sì ń dùn ń kẹ́dùn.+

 8 Ayọ̀ ìlù tanboríìnì ti dáwọ́ dúró;

Ariwo àwọn tó ń ṣe àríyá ti dópin;

Ìró ayọ̀ háàpù ti dáwọ́ dúró.+

 9 Wọ́n ń mu wáìnì láìsí orin,

Ọtí sì ń korò lẹ́nu àwọn tó ń mu ún.

10 Ìlú tí wọ́n pa tì ti wó lulẹ̀;+

Gbogbo ilé wà ní títì pa kí ẹnikẹ́ni má bàa wọlé.

11 Wọ́n ń kígbe ní àwọn ojú ọ̀nà torí wáìnì.

Gbogbo ìdùnnú ti pòórá;

Ayọ̀ ilẹ̀ náà ti lọ.+

12 Wọ́n fi ìlú náà sílẹ̀ ní àwókù;

Wọ́n ti wó ẹnubodè wómúwómú, ó ti di òkìtì àwókù.+

13 Bó ṣe máa rí ní ilẹ̀ náà nìyí, láàárín àwọn èèyàn náà:

Bí ìgbà tí wọ́n bá lu igi ólífì,+

Bí ìgbà tí wọ́n pèéṣẹ́* nígbà tí ìkórè èso àjàrà dópin.+

14 Wọ́n máa gbóhùn sókè,

Wọ́n máa kígbe ayọ̀.

Wọ́n máa kéde títóbi Jèhófà láti òkun.*+

15 Ìdí nìyẹn tí wọ́n fi máa yin Jèhófà lógo ní agbègbè ìmọ́lẹ̀;*+

Ní àwọn erékùṣù òkun, wọ́n máa yin orúkọ Jèhófà, Ọlọ́run Ísírẹ́lì lógo.+

16 À ń gbọ́ àwọn orin láti ìkángun ayé pé:

“Ògo ni fún Olódodo!”*+

Àmọ́ mo sọ pé: “Mò ń kú lọ, mò ń kú lọ!

Ó mà ṣe fún mi o! Àwọn ọ̀dàlẹ̀ ti dalẹ̀;

Ìwà ọ̀dàlẹ̀ wọn ni àwọn ọ̀dàlẹ̀ fi dalẹ̀.”+

17 Ìbẹ̀rù, kòtò àti pańpẹ́ ń dúró dè ọ́, ìwọ tó ń gbé ilẹ̀ náà.+

18 Ẹnikẹ́ni tó bá ń sá fún ìró ìbẹ̀rù á já sínú kòtò,

Pańpẹ́ sì máa mú ẹnikẹ́ni tó bá ń jáde látinú kòtò.+

Torí àwọn ibú omi ọ̀run máa ṣí,

Àwọn ìpìlẹ̀ ilẹ̀ sì máa mì tìtì.

19 Ilẹ̀ náà ti fọ́ sọ́tọ̀ọ̀tọ̀;

A ti mi ilẹ̀ náà jìgìjìgì;

Ilẹ̀ náà ń gbọ̀n rìrì.+

20 Ilẹ̀ náà ń ta gọ̀ọ́gọ̀ọ́ bí ẹni tó mutí yó,

Ó sì ń fì síwá sẹ́yìn bí ahéré nínú afẹ́fẹ́.

Ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ wà lórí rẹ̀, ó sì wúwo gan-an,+

Ó máa ṣubú, débi pé kò ní dìde mọ́.

21 Ní ọjọ́ yẹn, Jèhófà máa yíjú sí àwọn ọmọ ogun ibi gíga lókè

Àti sí àwọn ọba ayé lórí ilẹ̀.

22 A máa kó wọn jọ

Bí àwọn ẹlẹ́wọ̀n tí wọ́n kó jọ sínú kòtò,

A máa tì wọ́n pa mọ́ inú àjà ilẹ̀;

Lẹ́yìn ọ̀pọ̀ ọjọ́, a máa rántí wọn.

23 Òṣùpá àrànmọ́jú máa tẹ́,

Ojú sì máa ti oòrùn tó ń ràn,+

Torí Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun ti di Ọba+ ní Òkè Síónì+ àti ní Jerúsálẹ́mù,

Ògo rẹ̀ ń tàn níwájú àwọn àgbààgbà àwọn èèyàn rẹ̀.*+

25 Jèhófà, ìwọ ni Ọlọ́run mi.

Mo gbé ọ ga, mo yin orúkọ rẹ,

Torí o ti ṣe àwọn ohun àgbàyanu,+

Àwọn ohun tí o pinnu* láti ìgbà àtijọ́,+

Nínú òtítọ́,+ nínú ìfọkàntán.

 2 Torí o ti sọ ìlú kan di òkúta tí a tò jọ pelemọ,

O ti sọ ìlú olódi di ibi tí a rún wómúwómú.

Ilé gogoro àjèjì kì í ṣe ìlú mọ́;

Wọn ò ní tún un kọ́ láé.

 3 Ìdí nìyẹn tí àwọn èèyàn tó lágbára fi máa yìn ọ́ lógo;

Àwọn orílẹ̀-èdè oníkà máa bẹ̀rù rẹ.+

 4 Torí o ti di ibi ààbò fún ẹni rírẹlẹ̀,

Ibi ààbò fún aláìní nínú ìdààmú rẹ̀,+

Ibi ààbò kúrò lọ́wọ́ ìjì òjò,

Àti ibòji kúrò lọ́wọ́ ooru.+

Nígbà tí atẹ́gùn líle àwọn ìkà bá dà bí ìjì òjò tó kọ lu ògiri,

 5 Bí ooru ní ilẹ̀ tí kò lómi,

O dáwọ́ ariwo àwọn àjèjì dúró.

Bí òjìji ìkùukùu* ṣe ń lé ooru lọ,

Bẹ́ẹ̀ ni a máa mú kí orin àwọn ìkà dáwọ́ dúró.

 6 Lórí òkè yìí,+ Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun máa se àkànṣe àsè tó dọ́ṣọ̀+

Fún gbogbo èèyàn,

Àkànṣe àsè tó ní wáìnì tó dáa,*

Àsè tó dọ́ṣọ̀ tí mùdùnmúdùn kún inú rẹ̀,

Àsè tó ní wáìnì tó dáa tí wọ́n sẹ́.

 7 Lórí òkè yìí, ó máa mú ohun tó ń bo gbogbo èèyàn kúrò*

Àti aṣọ* tí wọ́n hun bo gbogbo orílẹ̀-èdè.

 8 Ó máa gbé ikú mì* títí láé,+

Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sì máa nu omijé kúrò ní ojú gbogbo èèyàn.+

Ó máa mú ẹ̀gàn àwọn èèyàn rẹ̀ kúrò ní gbogbo ayé,

Torí Jèhófà fúnra rẹ̀ ti sọ ọ́.

 9 Ní ọjọ́ yẹn, wọ́n máa sọ pé:

“Wò ó! Ọlọ́run wa nìyí!+

A ti gbẹ́kẹ̀ lé e,+

Ó sì máa gbà wá là.+

Jèhófà nìyí!

A ti gbẹ́kẹ̀ lé e.

Ẹ jẹ́ ká máa yọ̀, kí inú wa sì dùn torí ìgbàlà rẹ̀.”+

10 Torí ọwọ́ Jèhófà máa wà lórí òkè yìí,+

A sì máa tẹ Móábù mọ́lẹ̀ ní àyè rẹ̀+

Bíi pòròpórò tí wọ́n tẹ̀ mọ́ inú ajílẹ̀ tí wọ́n kó jọ.

11 Ó máa na ọwọ́ rẹ̀ jáde sínú rẹ̀

Bí ìgbà tí òmùwẹ̀ bá na ọwọ́ rẹ̀ jáde láti lúwẹ̀ẹ́,

Ó sì máa rẹ ìgbéraga rẹ̀ wálẹ̀,+

Pẹ̀lú bó ṣe ń gbé ọwọ́ rẹ̀ lọ́nà tó já fáfá.

12 Ó sì máa wó ìlú olódi rẹ lulẹ̀,

Pẹ̀lú àwọn ògiri gíga tí o fi ṣe ààbò;

Ó máa wó o palẹ̀, ó máa wó o lulẹ̀ pátápátá.

26 Ní ọjọ́ yẹn, wọ́n máa kọ orin yìí+ ní ilẹ̀ Júdà:+

“A ní ìlú tó lágbára.+

Ó fi ìgbàlà ṣe àwọn ògiri rẹ̀, ó sì fi mọ òkìtì yí i ká.+

 2 Ẹ ṣí àwọn ẹnubodè,+ kí orílẹ̀-èdè olódodo lè wọlé,

Orílẹ̀-èdè tó ń fìgbà gbogbo jẹ́ olóòótọ́.

 3 O máa dáàbò bo àwọn tó gbára lé ọ pátápátá;*

O máa fún wọn ní àlàáfíà tí kò lópin, +

Torí pé ìwọ ni wọ́n gbẹ́kẹ̀ lé.+

 4 Ẹ gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà títí láé,+

Torí pé Àpáta ayérayé ni Jáà* Jèhófà.+

 5 Torí ó ti rẹ àwọn tó ń gbé ibi gíga sílẹ̀, ìlú tó ga.

Ó rẹ̀ ẹ́ wálẹ̀,

Ó mú un wá sílẹ̀ pátápátá;

Ó mú un wá sínú iyẹ̀pẹ̀.

 6 Ẹsẹ̀ máa tẹ̀ ẹ́ mọ́lẹ̀,

Ẹsẹ̀ àwọn tí ìyà ń jẹ, ìṣísẹ̀ àwọn tó rẹlẹ̀.”

 7 Ọ̀nà àwọn olódodo tọ́.*

Torí pé o jẹ́ olóòótọ́,

O máa mú kí ọ̀nà àwọn olódodo dán mọ́rán.

 8 Bí a ṣe ń tọ ọ̀nà àwọn ìdájọ́ rẹ, Jèhófà,

Ìwọ la gbẹ́kẹ̀ lé.

Orúkọ rẹ àti ìrántí rẹ ń wù wá* gan-an.*

 9 Ní òru, gbogbo ọkàn* mi wà lọ́dọ̀ rẹ,

Àní, ẹ̀mí mi ń wá ọ ṣáá;+

Torí tí àwọn ìdájọ́ bá ti ọ̀dọ̀ rẹ wá sí ayé,

Àwọn tó ń gbé ilẹ̀ náà máa kọ́ òdodo.+

10 Tí a bá tiẹ̀ ṣojúure sí ẹni burúkú,

Kò ní kọ́ òdodo.+

Kódà ó máa hùwà burúkú ní ilẹ̀ ìwà títọ́,*+

Kò sì ní rí títóbi Jèhófà.+

11 Jèhófà, ọwọ́ rẹ wà lókè, ṣùgbọ́n wọn ò rí i.+

Wọ́n máa rí ìtara tí o ní fún àwọn èèyàn rẹ, ojú á sì tì wọ́n.

Àní, iná tó wà fún àwọn ọ̀tá rẹ máa jó wọn run.

12 Jèhófà, o máa fún wa ní àlàáfíà,+

Torí pé gbogbo ohun tí a ṣe,

Ìwọ lo bá wa ṣe é.

13 Jèhófà Ọlọ́run wa, àwọn ọ̀gá míì ti jẹ lé wa lórí yàtọ̀ sí ìwọ,+

Àmọ́, orúkọ rẹ nìkan là ń dá.+

14 Òkú ni wọ́n; wọn ò ní wà láàyè.

Ikú ti pa wọ́n,* wọn ò ní dìde.+

Torí o ti yíjú sí wọn,

Kí o lè pa wọ́n rẹ́, kí ẹnikẹ́ni má sì dárúkọ wọn mọ́.

15 O ti mú kí orílẹ̀-èdè náà tóbi sí i, Jèhófà,

O ti mú kí orílẹ̀-èdè náà tóbi sí i;

O ti ṣe ara rẹ lógo.+

O ti sún gbogbo ààlà ilẹ̀ náà síwájú gan-an.+

16 Jèhófà, wọ́n yíjú sí ọ nígbà wàhálà;

Wọ́n gbàdúrà sí ọ kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́ látọkàn wá nígbà tí o bá wọn wí.+

17 Bí aláboyún tó fẹ́ bímọ,

Tó ń rọbí, tó sì ń ké torí ó ń jẹ̀rora,

Bẹ́ẹ̀ ni a ṣe rí nítorí rẹ, Jèhófà.

18 A lóyún, a sì ní ìrora ìrọbí,

Àmọ́ ṣe ló dà bíi pé afẹ́fẹ́ la bí.

A ò mú ìgbàlà wá sí ilẹ̀ náà,

A ò sì bí ẹnì kankan tó máa gbé ilẹ̀ náà.

19 “Àwọn òkú rẹ máa wà láàyè.

Àwọn òkú mi* máa jíǹde.+

Ẹ jí, ẹ sì kígbe ayọ̀,

Ẹ̀yin tí ẹ̀ ń gbé inú iyẹ̀pẹ̀!+

Torí pé ìrì yín dà bí ìrì àárọ̀,*

Ilẹ̀ sì máa mú kí àwọn tí ikú ti pa* tún pa dà wà láàyè.*

20 Ẹ lọ, ẹ̀yin èèyàn mi, ẹ wọnú yàrá yín tó wà ní inú,

Kí ẹ sì ti àwọn ilẹ̀kùn yín mọ́ ara yín.+

Ẹ fi ara yín pa mọ́ fúngbà díẹ̀,

Títí ìbínú* náà fi máa kọjá lọ.+

21 Torí pé, wò ó! Jèhófà ń bọ̀ láti àyè rẹ̀,

Láti pe àwọn tó ń gbé ilẹ̀ náà pé kí wọ́n wá jẹ́jọ́ torí ẹ̀ṣẹ̀ wọn,

Ilẹ̀ náà sì máa tú ìtàjẹ̀sílẹ̀ rẹ̀ síta,

Kò ní lè bo àwọn èèyàn rẹ̀ tí wọ́n pa, bó ṣe ń ṣe tẹ́lẹ̀.”

27 Ní ọjọ́ yẹn, Jèhófà, tòun ti idà rẹ̀ tó mú, tó tóbi, tó sì lágbára,+

Máa yíjú sí Léfíátánì,* ejò tó ń yọ́ bọ́rọ́,

Sí Léfíátánì, ejò tó ń lọ́,

Ó sì máa pa ẹran ńlá tó wà nínú òkun.

 2 Ní ọjọ́ yẹn, ẹ kọrin fún obìnrin náà* pé:

“Ọgbà àjàrà tí wáìnì rẹ̀ ń yọ ìfófòó!+

 3 Èmi, Jèhófà ń dáàbò bò ó.+

Gbogbo ìgbà ni mò ń bomi rin ín.+

Mò ń dáàbò bò ó tọ̀sántòru,

Kí ẹnikẹ́ni má bàa ṣe é léṣe.+

 4 Mi ò bínú rárá.+

Ta ló máa wá fi àwọn igi ẹlẹ́gùn-ún àti èpò bá mi jagun?

Gbogbo wọn ni màá tẹ̀ mọ́lẹ̀, tí màá sì dáná sun pa pọ̀.

 5 Àìjẹ́ bẹ́ẹ̀, jẹ́ kó rọ̀ mọ́ ibi ààbò mi.

Kó wá bá mi ṣàdéhùn àlàáfíà;

Àní kó wá àlàáfíà pẹ̀lú mi.”

 6 Lọ́jọ́ iwájú, Jékọ́bù máa ta gbòǹgbò,

Ísírẹ́lì máa yọ ìtànná, ó máa rú jáde,+

Wọ́n sì máa fi irè oko kún ilẹ̀ náà.+

 7 Ṣé dandan ni kí a fi ẹgba ẹni tó ń lù ú nà án ni?

Àbí ṣé dandan ni kí a pa á bí àwọn èèyàn rẹ̀ tí wọ́n pa?

 8 Igbe tó ń dẹ́rù bani lo máa fi bá a fà á nígbà tí o bá lé e lọ.

Atẹ́gùn rẹ̀ tó le ló máa fi lé e jáde ní ọjọ́ afẹ́fẹ́ ìlà oòrùn.+

 9 Torí náà, báyìí la ṣe máa ṣètùtù fún ẹ̀ṣẹ̀ Jékọ́bù,+

Èyí sì ni ohun tó máa jèrè lẹ́kùn-ún rẹ́rẹ́ nígbà tí a bá mú ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ kúrò:

Ó máa ṣe gbogbo òkúta pẹpẹ

Bí òkúta ẹfun tí wọ́n lọ̀ lúúlúú,

Òpó òrìṣà* àti pẹpẹ tùràrí kankan ò sì ní ṣẹ́ kù.+

10 Torí wọ́n máa pa ìlú olódi tì;

Wọ́n máa pa àwọn ibi ìjẹko tì, wọ́n á sì fi í sílẹ̀ bí aginjù.+

Ibẹ̀ ni ọmọ màlúù á ti máa jẹko, tó sì máa dùbúlẹ̀ sí,

Ó sì máa jẹ àwọn ẹ̀ka rẹ̀.+

11 Nígbà tí àwọn ẹ̀ka igi rẹ̀ bá ti gbẹ,

Àwọn obìnrin máa wá ṣẹ́ wọn,

Wọ́n á sì fi dáná.

Torí àwọn èèyàn yìí ò ní òye.+

Ìdí nìyẹn tí Aṣẹ̀dá wọn ò fi ní ṣàánú wọn rárá,

Ẹni tó dá wọn ò sì ní ṣojúure kankan sí wọn.+

12 Ní ọjọ́ yẹn, Jèhófà máa lu èso jáde láti Odò* tó ń ṣàn títí dé Àfonífojì Íjíbítì,+ a sì máa kó yín jọ ní ọ̀kọ̀ọ̀kan, ẹ̀yin èèyàn Ísírẹ́lì.+ 13 Ní ọjọ́ yẹn, wọ́n máa fun ìwo ńlá kan,+ àwọn tó ń ṣègbé lọ ní ilẹ̀ Ásíríà+ àti àwọn tó fọ́n ká ní ilẹ̀ Íjíbítì+ máa wá, wọ́n á sì forí balẹ̀ fún Jèhófà ní òkè mímọ́, ní Jerúsálẹ́mù.+

28 Adé* ìgbéraga* àwọn ọ̀mùtípara Éfúrémù+ gbé

Àti ìtànná ẹwà ológo rẹ̀ tó ti ń rọ,

Tó wà ní orí àfonífojì ọlọ́ràá tó jẹ́ ti àwọn tí wáìnì ti kápá wọn!

 2 Wò ó! Jèhófà ní ẹnì kan tó lókun tó sì lágbára.

Bí ìjì yìnyín tó ń sán ààrá, ìjì apanirun,

Bí ìjì tó ń sán ààrá tó ń fa àkúnya omi tó bùáyà,

Ó máa fipá jù ú sílẹ̀.

 3 Wọ́n máa fi ẹsẹ̀ tẹ

Àwọn adé ìgbéraga* ti àwọn ọ̀mùtípara Éfúrémù mọ́lẹ̀.+

 4 Òdòdó ẹwà ológo rẹ̀ tó ti ń rọ,

Èyí tó wà ní orí àfonífojì ọlọ́ràá,

Máa dà bí àkọ́pọ́n èso ọ̀pọ̀tọ́ ṣáájú ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn.

Tí ẹnì kan bá rí i, ṣe ló máa gbé e mì ní gbàrà tó bá ti wà lọ́wọ́ rẹ̀.

5 Ní ọjọ́ yẹn, Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun máa di adé ológo àti òdòdó ẹ̀yẹ fún àwọn èèyàn rẹ̀ tó ṣẹ́ kù.+ 6 Ó máa di ẹ̀mí ìdájọ́ òdodo fún ẹni tó jókòó láti ṣe ìdájọ́, ó sì máa jẹ́ orísun agbára fún àwọn tó ń lé ogun sẹ́yìn ní ẹnubodè.+

 7 Àwọn yìí náà ṣìnà torí wáìnì;

Ohun mímu wọn tó ní ọtí ń mú kí wọ́n ta gọ̀ọ́gọ̀ọ́,

Àlùfáà àti wòlíì ti ṣìnà torí ọtí;

Wáìnì ò jẹ́ kí wọ́n mọ nǹkan tí wọ́n ń ṣe,

Ọtí wọn sì ń jẹ́ kí wọ́n ta gọ̀ọ́gọ̀ọ́;

Ìran wọn ń mú kí wọ́n ṣìnà,

Wọ́n sì ń kọsẹ̀ nínú ìdájọ́.+

 8 Torí pé èébì ẹlẹ́gbin kún àwọn tábìlì wọn,

Kò sí ibi tí kò sí.

 9 Ta ni èèyàn máa fún ní ìmọ̀,

Ta sì ni èèyàn máa ṣàlàyé ọ̀rọ̀ fún?

Ṣé àwọn tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ gba wàrà lẹ́nu wọn ni,

Àwọn tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ já lẹ́nu ọmú?

10 Torí ó jẹ́ “àṣẹ kan tẹ̀ lé òmíràn, àṣẹ kan tẹ̀ lé òmíràn,

Okùn tẹ̀ lé okùn, okùn tẹ̀ lé okùn,*+

Díẹ̀ níbí, díẹ̀ lọ́hùn-ún.”

11 Torí náà, ó máa bá àwọn èèyàn yìí sọ̀rọ̀ nípasẹ̀ àwọn tó ń kólòlò* tí wọ́n sì ń sọ èdè àjèjì.+ 12 Ó ti sọ fún wọn rí pé: “Ibi ìsinmi nìyí. Ẹ jẹ́ kí ẹni tó ti rẹ̀ sinmi; ibi ìtura nìyí,” àmọ́ wọn ò fetí sílẹ̀.+ 13 Torí náà, ohun tí ọ̀rọ̀ Jèhófà máa jẹ́ fún wọn ni pé:

“Àṣẹ kan tẹ̀ lé òmíràn, àṣẹ kan tẹ̀ lé òmíràn,

Okùn tẹ̀ lé okùn, okùn tẹ̀ lé okùn,*+

Díẹ̀ níbí, díẹ̀ lọ́hùn-ún,”

Kí wọ́n lè kọsẹ̀, kí wọ́n sì ṣubú sẹ́yìn

Tí wọ́n bá ń rìn,

Kí wọ́n lè ṣèṣe, kí wọ́n lè dẹkùn mú wọn, kí ọwọ́ sì tẹ̀ wọ́n.+

14 Torí náà, ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ Jèhófà, ẹ̀yin afọ́nnu,

Ẹ̀yin alákòóso àwọn èèyàn yìí ní Jerúsálẹ́mù,

15 Nítorí ẹ sọ pé:

“A ti bá Ikú dá májẹ̀mú,+

A sì ti bá Isà Òkú* ṣe àdéhùn.*

Tí omi tó ń ru gùdù bá ya kọjá lójijì,

Kò ní dé ọ̀dọ̀ wa,

Torí a ti fi irọ́ ṣe ibi ààbò wa,

A sì ti fi ara wa pa mọ́ sínú èké.”+

16 Torí náà, ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí:

“Wò ó, màá fi òkúta+ tí a ti dán wò ṣe ìpìlẹ̀ ní Síónì,

Òkúta igun ilé+ tó ṣeyebíye, ti ìpìlẹ̀ tó dájú.+

Ẹnikẹ́ni tó bá ní ìgbàgbọ́ kò ní bẹ̀rù.+

17 Màá fi ìdájọ́ òdodo ṣe okùn ìdíwọ̀n,+

Màá sì fi òdodo ṣe irinṣẹ́ tí a fi ń mú nǹkan tẹ́jú.*+

Yìnyín máa gbá ibi ààbò irọ́ lọ,

Omi sì máa kún bo ibi ìfarapamọ́.

18 Májẹ̀mú tí ẹ bá Ikú dá ò ní fìdí múlẹ̀ mọ́,

Àdéhùn tí ẹ sì bá Isà Òkú* ṣe ò ní lẹ́sẹ̀ nílẹ̀.+

Tí omi tó ń ru gùdù bá ya kọjá lójijì,

Ó máa pa yín rẹ́.

19 Ní gbogbo ìgbà tó bá ti ń kọjá,

Ó máa gbá yín lọ;+

Torí á máa kọjá ní àràárọ̀,

Ní ọ̀sán àti ní òru.

Ìbẹ̀rù nìkan ló máa jẹ́ kí ohun tí wọ́n gbọ́ yé wọn.”*

20 Torí pé ibùsùn ti kéré jù láti na ara,

Aṣọ tí wọ́n hun sì ti tẹ́ẹ́rẹ́ jù láti fi bora.

21 Torí Jèhófà máa dìde bó ṣe ṣe ní Òkè Pérásímù;

Ó máa gbéra sọ bó ṣe ṣe ní àfonífojì* tó wà nítòsí Gíbíónì,+

Kó lè ṣe ìṣe rẹ̀, ìṣe rẹ̀ tó ṣàjèjì,

Kó sì lè ṣe iṣẹ́ rẹ̀, iṣẹ́ rẹ̀ tó ṣàrà ọ̀tọ̀.+

22 Ní báyìí, ẹ má fini ṣe yẹ̀yẹ́,+

Ká má bàa tún mú kí àwọn ìdè yín le sí i,

Torí mo ti gbọ́ látọ̀dọ̀ Olúwa Ọba Aláṣẹ, Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun

Pé a ti pinnu láti pa gbogbo ilẹ̀ náà* run.+

23 Ẹ gbọ́, kí ẹ sì fetí sí ohùn mi;

Ẹ fiyè sílẹ̀, kí ẹ sì fetí sí ọ̀rọ̀ mi.

24 Ṣé ẹni tó ń túlẹ̀ máa ń fi gbogbo ọjọ́ túlẹ̀ kó tó fúnrúgbìn ni?

Ṣé á máa túlẹ̀, tí á sì máa fọ́ ilẹ̀ rẹ̀ sí wẹ́wẹ́ láìdáwọ́ dúró ni?+

25 Tó bá ti mú kí ilẹ̀ náà tẹ́jú,

Ṣebí ó máa fọ́n kúmínì dúdú, kó sì gbin kúmínì,

Ṣebí ó sì máa gbin àlìkámà,* jéró àti ọkà bálì sí àyè wọn

Àti ọkà sípẹ́ẹ̀tì+ sí eteetí ilẹ̀?

26 Torí Ó ń kọ́ ọ* ní ọ̀nà tó tọ́;

Ọlọ́run rẹ̀ ń fún un ní ìtọ́ni.+

27 Torí a kì í fi ohun tí wọ́n fi ń pakà fọ́ kúmínì dúdú,+

A kì í sì í yí àgbá kẹ̀kẹ́ lórí kúmínì.

Kàkà bẹ́ẹ̀, ọ̀pá la fi ń lu kúmínì dúdú,

Igi la sì fi ń lu kúmínì.

28 Ṣé èèyàn máa ń fọ́ ọkà kó lè fi ṣe búrẹ́dì ni?

Rárá, kì í pa ọkà náà láìdáwọ́ dúró;+

Nígbà tó bá sì fi àwọn ẹṣin rẹ̀ fa àgbá kẹ̀kẹ́ rẹ̀ lórí rẹ̀,

Kò ní fọ́ ọ.+

29 Ọ̀dọ̀ Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun ni èyí náà ti wá,

Ẹni tí ìmọ̀ràn* rẹ̀ jẹ́ àgbàyanu,

Tó sì gbé àwọn ohun ńlá ṣe.*+

29 “O gbé ìwọ Áríélì,* Áríélì, ìlú tí Dáfídì pàgọ́ sí!+

Ẹ máa bá a lọ lọ́dọọdún;

Ẹ máa ṣe àwọn àjọyọ̀+ ní àkókò wọn.

 2 Àmọ́ màá mú ìdààmú bá Áríélì,+

Ó máa ṣọ̀fọ̀, ó máa dárò,+

Ó sì máa dà bí ibi ìdáná pẹpẹ Ọlọ́run fún mi.+

 3 Màá pàgọ́ yí ọ ká,

Màá ṣe ọgbà láti dó tì ọ́,

Màá sì ṣe àwọn ohun tí màá fi gbógun tì ọ́.+

 4 A máa rẹ̀ ọ́ wálẹ̀;

Wàá máa sọ̀rọ̀ láti ilẹ̀,

Iyẹ̀pẹ̀ ò sì ní jẹ́ kí ọ̀rọ̀ rẹ ṣe kedere.

Ohùn rẹ á máa jáde látinú ilẹ̀+

Bí ohùn abẹ́mìílò,

Àwọn ọ̀rọ̀ rẹ á sì máa dún ṣíoṣío látinú iyẹ̀pẹ̀.

 5 Àwọn ọ̀tá* rẹ tó pọ̀ rẹpẹtẹ máa dà bí eruku lẹ́búlẹ́bú,+

Àwọn ìkà tó pọ̀ rẹpẹtẹ sì máa dà bí ìyàngbò* tó ń fẹ́ lọ.+

Ó sì máa ṣẹlẹ̀ lójijì, ká tó ṣẹ́jú pẹ́.+

 6 Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun máa fún ọ láfiyèsí

Pẹ̀lú ààrá, ìmìtìtì ilẹ̀ àti ariwo ńlá,

Pẹ̀lú ìjì, atẹ́gùn líle àti ọwọ́ iná tó ń jẹni run.”+

 7 Gbogbo orílẹ̀-èdè tó pọ̀ rẹpẹtẹ tí wọ́n ń gbógun ja Áríélì,+

Gbogbo àwọn tí wọ́n ń gbógun jà á,

Àwọn ilé gogoro tí wọ́n fi dó tì í,

Àti àwọn tó ń kó ìdààmú bá a,

Máa wá dà bí àlá, ìran òru.

 8 Àní, ó máa dà bí ìgbà tí ẹni tí ebi ń pa lá àlá pé òun ń jẹun,

Àmọ́ tó jí, tí ebi ṣì ń pa á*

Àti bí ìgbà tí ẹni tí òùngbẹ ń gbẹ lá àlá pé òun ń mu omi,

Àmọ́ tó jí, tó ti rẹ̀ ẹ́, tí òùngbẹ ṣì ń gbẹ ẹ́.*

Bó ṣe máa rí fún gbogbo orílẹ̀-èdè tó pọ̀ rẹpẹtẹ nìyí,

Àwọn tó gbógun ja Òkè Síónì.+

 9 Kí ẹnu yà yín, kí ẹ sì ṣe kàyéfì;+

Ẹ fọ́ ara yín lójú, kí ẹ sì fọ́jú.+

Wọ́n ti yó, àmọ́ kì í ṣe wáìnì ni wọ́n mu yó;

Wọ́n ń ta gọ̀ọ́gọ̀ọ́, àmọ́ kì í ṣe ọtí ló ń mú kí wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀.

10 Torí Jèhófà ti da ẹ̀mí oorun àsùnwọra lù yín;+

Ó ti pa ojú yín dé, ẹ̀yin wòlíì,+

Ó sì ti bo orí yín, ẹ̀yin aríran.+

11 Gbogbo ìran dà bí ọ̀rọ̀ inú ìwé tí a gbé èdìdì lé fún yín.+ Tí wọ́n bá fún ẹni tó mọ̀wé kà, tí wọ́n sọ pé: “Jọ̀ọ́, kà á sókè,” á sọ pé: “Mi ò lè kà á, torí wọ́n ti gbé èdìdì lé e.” 12 Tí wọ́n bá sì fún ẹni tí kò mọ̀wé kà ní ìwé náà, tí wọ́n sọ pé: “Jọ̀ọ́, kà á,” á sọ pé: “Mi ò lè kàwé rárá.”

13 Jèhófà sọ pé: “Àwọn èèyàn yìí ń fi ẹnu wọn sún mọ́ mi,

Wọ́n sì ń fi ètè wọn bọlá fún mi,+

Àmọ́ ọkàn wọn jìnnà gan-an sí mi;

Àṣẹ èèyàn tí wọ́n kọ́ wọn ló sì ń mú kí wọ́n máa bẹ̀rù mi.+

14 Torí náà, èmi ni Ẹni tó tún máa ṣe àwọn ohun àgbàyanu sí àwọn èèyàn yìí,+

Ohun àgbàyanu kan tẹ̀ lé òmíràn;

Ọgbọ́n àwọn ọlọ́gbọ́n wọn máa ṣègbé,

Òye àwọn olóye wọn sì máa fara pa mọ́.”+

15 Ó mà ṣe o, fún àwọn tó sapá gidigidi kí wọ́n lè fi ohun tí wọ́n fẹ́ ṣe* pa mọ́ fún Jèhófà.+

Ibi tó ṣókùnkùn ni wọ́n ti ṣe iṣẹ́ wọn,

Tí wọ́n ń sọ pé: “Ta ló rí wa,

Ta ló mọ̀ nípa wa?”+

16 Ẹ wo bí ẹ ṣe ń dorí nǹkan kodò!*

Ṣé ojú kan náà ló yẹ ká fi wo amọ̀kòkò àti amọ̀?+

Ṣé ó yẹ kí ohun tí a dá sọ nípa ẹni tó dá a pé:

“Òun kọ́ ló dá mi”?+

Ṣé ohun tí a ṣe sì máa ń sọ fún ẹni tó ṣe é pé:

“Kò fi òye hàn”?+

17 Kò ní pẹ́ rárá tí Lẹ́bánónì fi máa di ọgbà eléso,+

A sì máa ka ọgbà eléso náà sí igbó.+

18 Ní ọjọ́ yẹn, àwọn adití máa gbọ́ ọ̀rọ̀ inú ìwé náà,

Àwọn afọ́jú sì máa ríran látinú ìṣúdùdù àti òkùnkùn.+

19 Àwọn oníwà pẹ̀lẹ́ máa yọ̀ gidigidi nínú Jèhófà,

Àwọn tó sì jẹ́ aláìní láàárín àwọn èèyàn máa yọ̀ nínú Ẹni Mímọ́ Ísírẹ́lì.+

20 Torí pé ìkà èèyàn kò ní sí mọ́,

Òpin máa dé bá afọ́nnu,

Gbogbo àwọn tó sì wà lójúfò láti ṣe ìkà máa pa run,+

21 Àwọn tó ń fi ọ̀rọ̀ èké dá àwọn míì lẹ́bi,

Tí wọ́n ń dẹ pańpẹ́ sílẹ̀ de olùgbèjà* ní ẹnubodè ìlú+

Àti àwọn tó ń jiyàn tí kò lẹ́sẹ̀ nílẹ̀ láti fi ìdájọ́ òdodo du olódodo.+

22 Torí náà, ohun tí Jèhófà, ẹni tó ra Ábúráhámù pa dà,+ sọ fún ilé Jékọ́bù nìyí:

“Ojú ò ní ti Jékọ́bù mọ́,

Ojú rẹ̀ ò sì ní funfun mọ́.*+

23 Torí tó bá rí àwọn ọmọ rẹ̀,

Tí wọ́n jẹ́ iṣẹ́ ọwọ́ mi, ní àárín rẹ̀,+

Wọ́n máa sọ orúkọ mi di mímọ́;

Àní, wọ́n máa sọ Ẹni Mímọ́ Jékọ́bù di mímọ́,

Wọ́n sì máa bẹ̀rù Ọlọ́run Ísírẹ́lì gidigidi.+

24 Àwọn tó ní èrò tí kò tọ́* máa ní òye,

Àwọn tó ń ráhùn sì máa gba ìtọ́ni.”

30 “Àwọn alágídí ọmọ gbé,”+ ni Jèhófà wí,

“Àwọn tó ń ṣe ohun tí mi ò ní lọ́kàn,+

Tí wọ́n gbìmọ̀ pọ̀,* àmọ́ tí kì í ṣe nípasẹ̀ ẹ̀mí mi,

Kí wọ́n lè dá ẹ̀ṣẹ̀ kún ẹ̀ṣẹ̀.

 2 Wọ́n lọ sí Íjíbítì+ láì fọ̀rọ̀ lọ̀ mí,*+

Láti wá ààbò lọ sọ́dọ̀ Fáráò,*

Kí wọ́n sì fi òjìji Íjíbítì ṣe ibi ìsádi wọn!

 3 Àmọ́ ibi ààbò Fáráò máa dójú tì yín,

Òjìji Íjíbítì tí ẹ sì fi ṣe ibi ìsádi máa rẹ̀ yín wálẹ̀.+

 4 Torí àwọn ìjòyè rẹ̀ wà ní Sóánì,+

Àwọn aṣojú rẹ̀ sì ti dé Hánésì.

 5 Àwọn èèyàn tí kò lè ṣe wọ́n láǹfààní kankan

Máa dójú ti gbogbo wọn,

Àwọn tí kò ṣèrànwọ́ kankan, tí wọn ò sì ṣeni láǹfààní kankan,

Ìtìjú àti ẹ̀tẹ́ nìkan ni wọ́n ń mú wá.”+

6 Ọ̀rọ̀ ìkéde lòdì sí àwọn ẹranko gúúsù:

Wọ́n gba ilẹ̀ wàhálà àti ìnira kọjá,

Ilẹ̀ kìnnìún, kìnnìún tó ń ké ramúramù,

Paramọ́lẹ̀ àti ejò oníná tó ń fò,*

Wọ́n gbé ọrọ̀ wọn sí ẹ̀yìn àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́,

Àtàwọn ohun tí wọ́n fẹ́ lò sórí iké àwọn ràkúnmí.

Àmọ́ àwọn nǹkan yìí ò ní ṣe àwọn èèyàn náà láǹfààní.

 7 Torí ìrànlọ́wọ́ Íjíbítì ò wúlò rárá.+

Torí náà, mo pe ẹni yìí ní: “Ráhábù,+ tó jókòó jẹ́ẹ́.”

 8 “Ó yá, lọ, kọ ọ́ sára wàláà níṣojú wọn,

Kí o sì kọ ọ́ sínú ìwé,+

Kó lè wúlò lọ́jọ́ ọ̀la,

Láti jẹ́ ẹ̀rí tó máa wà títí láé.+

 9 Torí pé ọlọ̀tẹ̀ èèyàn ni wọ́n,+ àwọn ẹlẹ́tàn ọmọ,+

Àwọn ọmọ tí kò fẹ́ gbọ́ òfin* Jèhófà.+

10 Wọ́n ń sọ fún àwọn aríran pé, ‘Ẹ má ṣe ríran,’

Àti fún àwọn olùríran pé, ‘Ẹ má sọ àwọn ìran tó jẹ́ òótọ́ fún wa.+

Ọ̀rọ̀ dídùn* ni kí ẹ bá wa sọ; ìran ẹ̀tàn ni kí ẹ máa rí.+

11 Ẹ yà kúrò lọ́nà; ẹ fọ̀nà sílẹ̀.

Ẹ má fi Ẹni Mímọ́ Ísírẹ́lì síwájú wa mọ́.’”+

12 Torí náà, ohun tí Ẹni Mímọ́ Ísírẹ́lì sọ nìyí:

“Torí pé ẹ ò gba ọ̀rọ̀ yìí,+

Tí ẹ gbẹ́kẹ̀ lé jìbìtì àti ẹ̀tàn,

Tí ẹ sì gbára lé àwọn nǹkan yìí,+

13 Ẹ̀ṣẹ̀ yìí máa dà bí ògiri tó ti sán fún yín,

Bí ògiri gíga tó wú, tó máa tó wó,

Ó máa wó lójijì, ká tó ṣẹ́jú pẹ́.

14 Ó máa fọ́ bí ìṣà ńlá tó jẹ́ ti amọ̀kòkò,

Ó máa fọ́ túútúú débi pé kò ní sí àfọ́kù kankan,

Láti fi wa iná láti ibi ìdáná

Tàbí láti fi bu omi nínú adágún.”*

15 Torí ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ, Ẹni Mímọ́ Ísírẹ́lì, sọ nìyí:

“Tí ẹ bá pa dà sọ́dọ̀ mi, tí ẹ sì sinmi, ẹ máa rígbàlà;

Ẹ máa lágbára tí ẹ bá fara balẹ̀, tí ẹ sì gbẹ́kẹ̀ lé mi.”+

Àmọ́ kò wù yín.+

16 Dípò ìyẹn, ẹ sọ pé: “Rárá, a máa gun ẹṣin sá lọ!”

Ẹ sì máa sá lọ lóòótọ́.

“A máa gun àwọn ẹṣin tó ń yára kánkán!”+

Àwọn tó ń lépa yín sì máa yára kánkán.+

17 Ẹgbẹ̀rún kan (1,000) máa gbọ̀n rìrì nítorí ìhàlẹ̀ ẹnì kan;+

Ìhàlẹ̀ ẹni márùn-ún máa mú kí ẹ sá,

Títí ohun tó ṣẹ́ kù nínú yín fi máa dà bí òpó lórí òkè ńlá,

Bí òpó tí wọ́n fi ṣe àmì lórí òkè kékeré.+

18 Àmọ́ Jèhófà ń fi sùúrù dúró* láti ṣojúure sí yín,+

Ó sì máa dìde láti ṣàánú yín.+

Torí pé Ọlọ́run ìdájọ́ òdodo ni Jèhófà.+

Aláyọ̀ ni gbogbo àwọn tó ń retí rẹ̀.*+

19 Tí àwọn èèyàn bá ń gbé ní Síónì, ní Jerúsálẹ́mù,+ o ò ní sunkún rárá.+ Ó dájú pé ó máa ṣojúure sí ọ tí o bá kígbe fún ìrànlọ́wọ́; ó máa dá ọ lóhùn ní gbàrà tó bá gbọ́ ọ.+ 20 Bó tiẹ̀ jẹ́ pé Jèhófà máa fi wàhálà ṣe oúnjẹ fún yín, tó sì máa fi ìyà ṣe omi fún yín,+ Olùkọ́ rẹ Atóbilọ́lá ò ní fi ara rẹ̀ pa mọ́ bíi ti tẹ́lẹ̀, o sì máa fi ojú ara rẹ rí Olùkọ́ rẹ Atóbilọ́lá.+ 21 Etí rẹ sì máa gbọ́ ọ̀rọ̀ kan lẹ́yìn rẹ pé, “Èyí ni ọ̀nà.+ Ẹ máa rìn nínú rẹ̀,” tó bá ṣẹlẹ̀ pé ẹ yà sí apá ọ̀tún tàbí tó bá ṣẹlẹ̀ pé ẹ yà sí apá òsì.+

22 Ẹ ó sọ fàdákà tí ẹ fi bo àwọn ère gbígbẹ́ yín àti wúrà tí ẹ fi bo àwọn ère onírin*+ yín di aláìmọ́. Ẹ ó sọ wọ́n nù bí aṣọ tí wọ́n fi ṣe nǹkan oṣù, ẹ ó sì sọ fún wọn pé: “A ò fẹ́ mọ́!”*+ 23 Ó máa rọ òjò sí ohun tí o gbìn sínú ilẹ̀,+ oúnjẹ tí ilẹ̀ bá sì mú jáde máa pọ̀ rẹpẹtẹ, ó sì máa lọ́ràá.*+ Ní ọjọ́ yẹn, ẹran ọ̀sìn rẹ máa jẹko ní àwọn pápá tó fẹ̀.+ 24 Àwọn màlúù àti àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ tó ń ṣiṣẹ́ lórí ilẹ̀ máa jẹ oúnjẹ ẹran tí wọ́n fi ewéko olómi-kíkan sí, èyí tí wọ́n fi ṣọ́bìrì àti àmúga fẹ́. 25 Odò àti ipadò máa wà lórí gbogbo òkè ńlá tó rí gogoro àti gbogbo òkè kéékèèké tó ga,+ ní ọjọ́ tí a pa wọ́n lọ rẹpẹtẹ tí àwọn ilé gogoro bá ṣubú. 26 Ìmọ́lẹ̀ òṣùpá àrànmọ́jú máa dà bí ìmọ́lẹ̀ oòrùn; ìmọ́lẹ̀ oòrùn sì máa lágbára sí i ní ìlọ́po méje,+ bí ìmọ́lẹ̀ ọjọ́ méje, ní ọjọ́ tí Jèhófà bá di àfọ́kù àwọn èèyàn rẹ̀,*+ tó sì wo ọgbẹ́ ńlá tó dá sí wọn lára nígbà tó kọ lù wọ́n sàn.+

27 Wò ó! Orúkọ Jèhófà ń bọ̀ láti ọ̀nà jíjìn,

Inú ń bí i gan-an, ó sì ń bọ̀ pẹ̀lú àwọsánmà* tó ṣú bolẹ̀.

Ìbínú kún ètè rẹ̀,

Ahọ́n rẹ̀ sì dà bí iná tó ń jẹni run.+

28 Ẹ̀mí* rẹ̀ dà bí àkúnya ọ̀gbàrá tó muni dé ọrùn,

Láti mi àwọn orílẹ̀-èdè jìgìjìgì nínú ajọ̀ ìparun;*

Ìjánu sì máa wà ní páárì àwọn èèyàn+ náà láti kó wọn ṣìnà.

29 Àmọ́ orin yín máa dà bí èyí tí wọ́n kọ ní òru

Nígbà tí ẹ̀ ń múra sílẹ̀* fún àjọyọ̀,+

Inú yín sì máa dùn bíi ti ẹni

Tó ń rìn tòun ti fèrè*

Bó ṣe ń lọ sí òkè Jèhófà, sọ́dọ̀ Àpáta Ísírẹ́lì.+

30 Jèhófà máa mú kí a gbọ́ ohùn rẹ̀ tó gbayì,+

Ó sì máa fi apá rẹ̀ hàn+ bó ṣe ń fi ìbínú tó le sọ̀ kalẹ̀ bọ̀,+

Pẹ̀lú ọwọ́ iná tó ń jẹni run,+

Òjò líle tó bẹ̀rẹ̀ lójijì,+ ìjì tó ń sán ààrá àti àwọn òkúta yìnyín.+

31 Nítorí ohùn Jèhófà, jìnnìjìnnì máa bo Ásíríà;+

Ó máa fi ọ̀pá lù ú.+

32 Gbogbo bó ṣe ń fi ọ̀pá rẹ̀ tó fi ń jẹni níyà,

Èyí tí Jèhófà máa mú wá sórí Ásíríà,

Máa jẹ́ pẹ̀lú àwọn ìlù tanboríìnì àti háàpù,+

Bó ṣe ń fi ọwọ́ rẹ̀ sí wọn lójú ogun.+

33 Torí pé ó ti múra Tófétì*+ rẹ̀ sílẹ̀;

Ó ti múra rẹ̀ sílẹ̀ fún ọba pẹ̀lú.+

Ó ti to igi jọ pelemọ, ó sì fẹ̀,

Pẹ̀lú iná tó ń jó lala àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ igi.

Èémí Jèhófà, tó dà bí ọ̀gbàrá imí ọjọ́,

Máa dáná sí i.

31 Ó mà ṣe fún àwọn tó ń wá ìrànlọ́wọ́ lọ sọ́dọ̀ Íjíbítì o,+

Tí wọ́n gbójú lé ẹṣin,+

Tí wọ́n gbẹ́kẹ̀ lé kẹ̀kẹ́ ogun, torí pé wọ́n pọ̀,

Àti àwọn ẹṣin ogun,* torí pé wọ́n lágbára.

Wọn ò yíjú sí Ẹni Mímọ́ Ísírẹ́lì,

Wọn ò sì wá Jèhófà.

 2 Àmọ́ òun náà gbọ́n, ó sì máa mú àjálù wá,

Kò sì ní kó ọ̀rọ̀ ara rẹ̀ jẹ.

Ó máa dìde sí ilé àwọn tó ń ṣe ohun tó burú

Àti sí àwọn tó ń ran aṣebi lọ́wọ́.+

 3 Àmọ́ èèyàn lásán ni àwọn ará Íjíbítì, wọn kì í ṣe Ọlọ́run;

Ẹran ara ni àwọn ẹṣin wọn ní, wọn kì í ṣe ẹ̀mí.+

Tí Jèhófà bá na ọwọ́ rẹ̀,

Ẹnikẹ́ni tó bá ranni lọ́wọ́ máa kọsẹ̀,

Ẹnikẹ́ni tí wọ́n bá sì ràn lọ́wọ́ máa ṣubú;

Gbogbo wọn máa ṣègbé lẹ́ẹ̀kan náà.

 4 Torí ohun tí Jèhófà sọ fún mi nìyí:

“Bí kìnnìún, ìyẹn ọmọ kìnnìún tó lágbára,* ṣe ń kùn lórí ẹran tó pa,

Nígbà tí a pe odindi àwùjọ àwọn olùṣọ́ àgùntàn sí i,

Tí ohùn wọn ò dẹ́rù bà á,

Tí gìrìgìrì wọn ò sì kó jìnnìjìnnì bá a,

Bẹ́ẹ̀ ni Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun máa sọ̀ kalẹ̀ wá ja ogun

Lórí Òkè Síónì àti lórí òkè kékeré rẹ̀.

 5 Bí àwọn ẹyẹ tó ń já ṣòòrò wálẹ̀, ni Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun ṣe máa gbèjà Jerúsálẹ́mù.+

Ó máa gbèjà rẹ̀, ó sì máa gbà á là.

Ó máa dá a sí, ó sì máa gbà á sílẹ̀.”

6 “Ẹ pa dà sọ́dọ̀ Ẹni tí ẹ fi àfojúdi ṣọ̀tẹ̀ sí, ẹ̀yin èèyàn Ísírẹ́lì.+ 7 Torí pé ní ọjọ́ yẹn, kálukú máa kọ àwọn ọlọ́run rẹ̀ tí kò ní láárí, tó fi fàdákà ṣe àti àwọn ọlọ́run rẹ̀ tí kò wúlò, tó fi wúrà ṣe, èyí tí ẹ fi ọwọ́ ara yín ṣe, tó sì jẹ́ ẹ̀ṣẹ̀.

 8 Ará Ásíríà máa tipa idà tí kì í ṣe ti èèyàn ṣubú;

Idà tí kì í ṣe ti aráyé ló sì máa jẹ ẹ́ run.+

Ó máa sá lọ nítorí idà,

Wọ́n sì máa fipá kó àwọn ọ̀dọ́kùnrin rẹ̀ ṣiṣẹ́.

 9 Àpáta rẹ̀ máa kọjá lọ torí ìbẹ̀rù tó bò ó,

Jìnnìjìnnì sì máa bá àwọn ìjòyè rẹ̀ torí òpó tí a fi ṣe àmì,” ni Jèhófà wí,

Ẹni tí ìmọ́lẹ̀* rẹ̀ wà ní Síónì, tí iná ìléru rẹ̀ sì wà ní Jerúsálẹ́mù.

32 Wò ó! Ọba+ kan máa jẹ fún òdodo,+

Àwọn ìjòyè sì máa ṣàkóso fún ìdájọ́ òdodo.

 2 Ẹnì kọ̀ọ̀kan máa dà bí ibi tó ṣeé fara pa mọ́ sí* kúrò lọ́wọ́ ẹ̀fúùfù,

Ibi ààbò* kúrò lọ́wọ́ ìjì òjò,

Bí omi tó ń ṣàn ní ilẹ̀ tí kò lómi,+

Bí òjìji àpáta ńlá ní ilẹ̀ tó gbẹ táútáú.

 3 Ojú àwọn tó ń ríran kò ní lẹ̀ pọ̀ mọ́,

Etí àwọn tó ń gbọ́ràn sì máa ṣí sílẹ̀.

 4 Ọkàn àwọn tí kì í fara balẹ̀ máa ronú nípa ìmọ̀,

Ahọ́n tó sì ń kólòlò máa sọ̀rọ̀ tó já geere, tó sì ṣe kedere.+

 5 Wọn ò tún ní pe aláìnírònú ní ọ̀làwọ́ mọ́,

Wọn ò sì ní pe oníwàkiwà ní èèyàn pàtàkì mọ́;

 6 Torí aláìnírònú máa sọ̀rọ̀ òmùgọ̀,

Ọkàn rẹ̀ sì máa gbèrò ibi,+

Láti gbé ìpẹ̀yìndà lárugẹ,* kó sì máa sọ ọ̀rọ̀kọrọ̀ sí Jèhófà,

Láti mú kí ẹni tí ebi ń pa* wà láìjẹun,

Kó sì fi ohun mímu du ẹni tí òùngbẹ ń gbẹ.

 7 Ohun búburú ni ọkùnrin oníwàkíwà ń gbèrò;+

Ìwà àìnítìjú ló ń gbé lárugẹ,

Kó lè fi irọ́ ba ti ẹni tí ìyà ń jẹ jẹ́,+

Kódà nígbà tí aláìní bá ń sọ ohun tó tọ́.

 8 Àmọ́ èrò ọ̀làwọ́ ló wà lọ́kàn ẹni tó lawọ́;

Kì í sì í jáwọ́ nínú àwọn ìṣe ọ̀làwọ́.*

 9 “Ẹ̀yin obìnrin tí ara tù, ẹ dìde, kí ẹ fetí sí ohùn mi!

Ẹ̀yin ọmọbìnrin+ tí ẹ ò ka nǹkan sí, ẹ fiyè sí ohun tí mò ń sọ!

10 Láàárín ọdún kan ó lé díẹ̀, jìnnìjìnnì máa bá ẹ̀yin tí ẹ ò ka nǹkan sí,

Torí a ò ní tíì kó èso kankan jọ nígbà tí ìkórè èso àjàrà bá dópin.+

11 Ẹ wárìrì, ẹ̀yin obìnrin tí ara tù!

Ẹ gbọ̀n jìnnìjìnnì, ẹyin tí kò ka nǹkan sí!

Ẹ bọ́ra yín sí ìhòòhò,

Kí ẹ sì ró aṣọ ọ̀fọ̀* mọ́ ìbàdí yín.+

12 Ẹ lu ọmú yín bí ẹ ṣe ń dárò

Torí àwọn pápá tí ẹ fẹ́ràn àti àjàrà tó ń méso jáde.

13 Torí ẹ̀gún àti òṣùṣú máa bo ilẹ̀ àwọn èèyàn mi;

Wọ́n máa bo gbogbo ilé tí wọ́n ti ń yọ̀,

Àní, ìlú tó ń yọ̀ gidigidi.+

14 Torí wọ́n ti pa ilé gogoro tó láàbò tì;

Wọ́n ti pa ìlú aláriwo tì.+

Ófélì+ àti ilé ìṣọ́ ti di ahoro títí láé,

Ààyò àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ igbó,

Ibi ìjẹko àwọn agbo ẹran,+

15 Títí dìgbà tí a bá tú ẹ̀mí jáde sórí wa látòkè,+

Tí aginjù di ọgbà eléso,

Tí a sì ka ọgbà eléso sí igbó.+

16 Ìdájọ́ òdodo á wá máa gbé ní aginjù,

Òdodo á sì máa gbé inú ọgbà eléso.+

17 Àlàáfíà ni òdodo tòótọ́ máa mú wá, +

Èso òdodo tòótọ́ sì máa jẹ́ ìparọ́rọ́ àti ààbò tó máa wà pẹ́ títí.+

18 Ibi tí àlàáfíà ti jọba làwọn èèyàn mi á máa gbé,

Nínú àwọn ibi tó ní ààbò àtàwọn ibi ìsinmi tó pa rọ́rọ́.+

19 Àmọ́ yìnyín máa mú kí igbó tẹ́ pẹrẹsẹ,

Ìlú sì máa di ibi tó tẹ́jú pátápátá.

20 Aláyọ̀ ni ẹ̀yin tí ẹ̀ ń fún irúgbìn sétí gbogbo omi,

Tí ẹ̀ ń rán akọ màlúù àti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ jáde.”*+

33 O gbé, ìwọ apanirun tí wọn ò tíì pa run;+

Ìwọ ọ̀dàlẹ̀ tí wọn ò tíì dalẹ̀ rẹ̀!

Tí o bá pani run tán, wọ́n á pa ìwọ náà run.+

Tí o bá dalẹ̀ tán, wọ́n á dalẹ̀ ìwọ náà.

 2 Jèhófà, ṣojúure sí wa.+

Ìwọ la gbẹ́kẹ̀ lé.

Di apá* wa+ ní àràárọ̀,

Àní, ìgbàlà wa ní àkókò wàhálà.+

 3 Tí àwọn èèyàn bá gbọ́ ìro ìdàrúdàpọ̀, wọ́n á sá lọ.

Tí o bá dìde, àwọn orílẹ̀-èdè á fọ́n ká.+

 4 Bí ọ̀yànnú eéṣú ṣe ń kóra jọ la máa kó àwọn ẹrù ogun rẹ jọ;

Àwọn èèyàn máa rọ́ bò ó bí ọ̀wọ́ eéṣú.

 5 A máa gbé Jèhófà ga,

Torí ó ń gbé ibi gíga lókè.

Ó máa fi ìdájọ́ tí ó tọ́ àti òdodo kún Síónì.

 6 Òun ló ń mú kí nǹkan lọ bó ṣe yẹ láwọn àkókò rẹ;

Ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ ìgbàlà,+ ọgbọ́n, ìmọ̀ àti ìbẹ̀rù Jèhófà,+

Èyí ni ohun iyebíye rẹ̀.

 7 Wò ó! Àwọn akọni wọn ń ké jáde lójú ọ̀nà;

Àwọn ìránṣẹ́ àlàáfíà ń sunkún gidigidi.

 8 Àwọn ojú pópó dá páropáro;

Ẹnì kankan ò gba àwọn ojú ọ̀nà kọjá.

Ó* ti da májẹ̀mú;

Ó ti kọ àwọn ìlú náà sílẹ̀;

Kò ka ẹni kíkú sí.+

 9 Ilẹ̀ náà ń ṣọ̀fọ̀,* kò sì lọ́ràá mọ́.

Ojú ti Lẹ́bánónì;+ ó ti jẹrà.

Ṣárónì ti dà bí aṣálẹ̀,

Báṣánì àti Kámẹ́lì sì gbọn ewé wọn dà nù.+

10 “Ní báyìí, màá dìde,” ni Jèhófà wí,

“Ní báyìí, màá gbé ara mi ga;+

Ní báyìí, màá ṣe ara mi lógo.

11 Ẹ lóyún koríko gbígbẹ, ẹ sì bí àgékù pòròpórò.

Ẹ̀mí yín máa jẹ yín run bí iná.+

12 Àwọn èèyàn sì máa dà bí ẹfun tó jóná.

Wọ́n máa dáná sun wọ́n bí ẹ̀gún tí a gé lulẹ̀.+

13 Ẹ̀yin tí ẹ wà níbi tó jìnnà, ẹ gbọ́ ohun tí màá ṣe!

Ẹ̀yin tí ẹ sì wà nítòsí, ẹ mọ agbára mi!

14 Jìnnìjìnnì ti bá àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ ní Síónì;+

Àwọn apẹ̀yìndà ń gbọ̀n rìrì:

‘Èwo nínú wa ló lè gbé níbi tí iná tó ń jẹni run wà?+

Èwo nínú wa ló lè bá ọwọ́ iná tí kò ṣeé pa gbé?’

15 Ẹni tí kò jáwọ́ nínú ṣíṣe òdodo,+

Tó ń sọ ohun tó tọ́,+

Tó kọ àìṣòótọ́ àti èrè jìbìtì,

Tí ọwọ́ rẹ̀ kọ àbẹ̀tẹ́lẹ̀ dípò kó gbà á,+

Tó ń di etí rẹ̀ sí ọ̀rọ̀ ìtàjẹ̀sílẹ̀,

Tó sì ń di ojú rẹ̀ kó má bàa rí ohun tó burú

16 —Ó máa gbé ní àwọn ibi gíga;

Ibi ààbò rẹ̀* máa wà níbi àwọn àpáta tó láàbò,

Á máa rí oúnjẹ jẹ,

Omi ò sì ní wọ́n ọn láé.”+

17 Ojú rẹ máa rí ọba kan nínú ẹwà rẹ̀;

Wọ́n máa rí ilẹ̀ kan tó jìnnà réré.

18 O máa rántí* ìbẹ̀rù náà nínú ọkàn rẹ:

“Ibo ni akọ̀wé wà?

Ibo ni ẹni tó wọn ìṣákọ́lẹ̀* wà?+

Ibo ni ẹni tó ka àwọn ilé gogoro wà?”

19 O ò ní rí àwọn aláfojúdi èèyàn mọ́,

Àwọn èèyàn tí èdè wọn ṣòroó lóye* gan-an,

Tí ahọ́n wọn tó ń kólòlò kò lè yé ọ.+

20 Wo Síónì, ìlú àwọn àjọyọ̀ wa!+

Ojú rẹ máa rí Jerúsálẹ́mù bí ibùgbé tó pa rọ́rọ́,

Àgọ́ tí wọn ò ní kó kúrò.+

Wọn ò ní fa àwọn èèkàn àgọ́ rẹ̀ yọ láé,

Wọn ò sì ní já ìkankan nínú àwọn okùn rẹ̀.

21 Àmọ́ níbẹ̀, Jèhófà, Ọba Ọlọ́lá,

Máa jẹ́ agbègbè odò fún wa, èyí tó ní àwọn ipadò tó fẹ̀,

Tí ọ̀wọ́ àwọn ọkọ̀ òkun kankan kò ní lọ síbẹ̀,

Tí ọkọ̀ òkun ńlá kankan kò sì ní gba ibẹ̀ kọjá.

22 Torí Jèhófà ni Onídàájọ́ wa,+

Jèhófà ni Afúnnilófin wa,+

Jèhófà ni Ọba wa;+

Òun ni Ẹni tó máa gbà wá.+

23 Àwọn okùn rẹ máa rọ̀ dirodiro;

Wọn ò lè gbé òpó dúró, wọn ò sì lè ta ìgbòkun.

Nígbà yẹn, wọ́n máa pín ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ ẹrù ogun;

Arọ pàápàá máa kó ẹrù ogun púpọ̀.+

24 Kò sí ẹnì kankan tó ń gbé ibẹ̀* tó máa sọ pé: “Ara mi ò yá.”+

A ti máa dárí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn èèyàn tó ń gbé ilẹ̀ náà jì wọ́n.+

34 Ẹ sún mọ́ tòsí kí ẹ lè gbọ́, ẹ̀yin orílẹ̀-èdè,

Kí ẹ sì fetí sílẹ̀, ẹ̀yin èèyàn.

Kí ayé àti ohun tó kún inú rẹ̀ fetí sílẹ̀,

Ilẹ̀ àti gbogbo èso rẹ̀.

 2 Torí Jèhófà ń bínú sí gbogbo orílẹ̀-èdè,+

Inú rẹ̀ sì ń ru sí gbogbo àwọn ọmọ ogun wọn.+

Ó máa pa wọ́n run;

Ó máa pa wọ́n lọ rẹpẹtẹ.+

 3 A máa ju àwọn èèyàn tí a pa síta,

Òórùn burúkú àwọn òkú wọn sì máa ròkè;+

Àwọn òkè máa yọ́ nítorí ẹ̀jẹ̀ wọn.*+

 4 Gbogbo ọmọ ogun ọ̀run máa jẹrà dà nù,

A sì máa ká ọ̀run jọ bí àkájọ ìwé.

Gbogbo ọmọ ogun wọn máa rọ dà nù,

Bí ewé tó ti rọ ṣe ń já bọ́ lára àjàrà

Àti bí èso ọ̀pọ̀tọ́ tó ti bà jẹ́ ṣe ń já bọ́ lára igi ọ̀pọ̀tọ́.

 5 “Torí idà mi máa rin gbingbin ní ọ̀run.+

Ó máa sọ̀ kalẹ̀ sórí Édómù láti ṣèdájọ́,+

Sórí àwọn èèyàn tí màá pa run.

 6 Jèhófà ní idà kan; ẹ̀jẹ̀ máa bò ó.

Ọ̀rá+ máa bò ó,

Ẹ̀jẹ̀ àwọn ọmọ àgbò àti ewúrẹ́ máa bò ó,

Ọ̀rá kíndìnrín àwọn àgbò máa bò ó.

Torí pé Jèhófà ní ẹbọ ní Bósírà,

Ó máa pa ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ ní ilẹ̀ Édómù.+

 7 Àwọn akọ màlúù igbó máa bá wọn sọ̀ kalẹ̀,

Àwọn akọ ọmọ màlúù pẹ̀lú àwọn alágbára.

Ẹ̀jẹ̀ máa rin ilẹ̀ wọn gbingbin,

Ọ̀rá sì máa rin iyẹ̀pẹ̀ wọn gbingbin.”

 8 Torí Jèhófà ní ọjọ́ ẹ̀san,+

Ọdún ẹ̀san torí ẹjọ́ lórí Síónì.+

 9 Àwọn odò rẹ̀* máa yí pa dà di ọ̀dà bítúmẹ́nì rírọ̀,

Iyẹ̀pẹ̀ rẹ̀ máa di imí ọjọ́,

Ilẹ̀ rẹ̀ sì máa dà bí ọ̀dà bítúmẹ́nì rírọ̀ tó ń jó.

10 A ò ní pa á, ní òru tàbí ní ọ̀sán;

Èéfín rẹ̀ á máa ròkè títí láé.

Ibi ìparun ló máa jẹ́ láti ìran dé ìran;

Kò sẹ́ni tó máa gba ibẹ̀ kọjá títí láé àti láéláé.+

11 Ẹyẹ òfú àti òòrẹ̀ á máa gbé ibẹ̀,

Àwọn òwìwí elétí gígùn àti àwọn ẹyẹ ìwò á máa gbé inú rẹ̀.

Ó máa na okùn ìdíwọ̀n òfìfo sórí rẹ̀

Àti okùn ìwọ̀n, láti sọ ọ́ di ahoro.*

12 Wọn ò ní pe ìkankan nínú àwọn èèyàn rẹ̀ pàtàkì wá jọba,

Gbogbo ìjòyè rẹ̀ ò sì ní já mọ́ nǹkan kan mọ́.

13 Ẹ̀gún máa hù nínú àwọn ilé gogoro rẹ̀ tó láàbò,

Èsìsì àti èpò ẹlẹ́gùn-ún máa hù nínú àwọn ibi ààbò rẹ̀.

Ó máa di ilé àwọn ajáko,*+

Ibi àkámọ́ àwọn ògòǹgò.

14 Àwọn ẹranko inú aṣálẹ̀ máa pàdé àwọn ẹranko tó ń hu,

Ewúrẹ́ igbó* sì máa ké sí èkejì rẹ̀.

Àní, ibẹ̀ ni ẹyẹ aáṣẹ̀rẹ́ máa wọ̀ sí, tó sì ti máa rí ibi ìsinmi.

15 Ibẹ̀ ni ejò ọlọ́fà máa kọ́ ìtẹ́ rẹ̀ sí, tó sì máa yé ẹyin sí,

Ó máa pa ẹyin, ó sì máa kó wọn jọ sábẹ́ òjìji rẹ̀.

Àní, ibẹ̀ ni àwọn àwòdì máa kóra jọ sí, kálukú pẹ̀lú èkejì rẹ̀.

16 Ẹ wá a nínú ìwé Jèhófà, kí ẹ sì kà á sókè:

A ò ní wá ìkankan nínú wọn tì;

Èyíkéyìí nínú wọn ò ní ṣaláìní ẹnì kejì,

Torí pé ẹnu Jèhófà ni àṣẹ náà ti wá,

Ẹ̀mí rẹ̀ ló sì kó wọn jọ.

17 Òun ni Ẹni tó ṣẹ́ kèké fún wọn,

Ọwọ́ rẹ̀ sì ti wọn ibi tí a yàn fún wọn.*

Ó máa jẹ́ tiwọn títí láé;

Ibẹ̀ ni wọ́n á máa gbé láti ìran dé ìran.

35 Aginjù àti ilẹ̀ tí kò lómi máa yọ̀,+

Aṣálẹ̀ tó tẹ́jú máa yọ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀, ó sì máa yọ ìtànná bíi sáfúrónì.+

 2 Ó dájú pé ó máa yọ ìtànná;+

Ó máa yọ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀, ó sì máa kígbe ayọ̀.

A máa fún un ní ògo Lẹ́bánónì,+

Ẹwà Kámẹ́lì+ àti ti Ṣárónì.+

Wọ́n máa rí ògo Jèhófà, ẹwà Ọlọ́run wa.

 3 Ẹ fún àwọn ọwọ́ tí kò lágbára lókun,

Ẹ sì mú kí àwọn orúnkún tó ń gbọ̀n dúró gbọn-in.+

 4 Ẹ sọ fún àwọn tó ń ṣàníyàn nínú ọkàn wọn pé:

“Ẹ jẹ́ alágbára. Ẹ má bẹ̀rù.

Ẹ wò ó! Ọlọ́run yín máa wá gbẹ̀san,

Ọlọ́run máa wá láti fìyà ẹ̀ṣẹ̀ jẹni.+

Ó máa wá gbà yín sílẹ̀.”+

 5 Ní àkókò yẹn, ojú àwọn afọ́jú máa là,+

Etí àwọn adití sì máa ṣí.+

 6 Ní àkókò yẹn, ẹni tó yarọ máa fò sókè bí àgbọ̀nrín,+

Ahọ́n ẹni tí kò lè sọ̀rọ̀ sì máa kígbe ayọ̀.+

Torí omi máa tú jáde ní aginjù,

Odò sì máa ṣàn ní aṣálẹ̀ tó tẹ́jú.

 7 Ilẹ̀ tí ooru ti mú kó gbẹ táútáú máa di adágún omi tí esùsú* kún inú rẹ̀,

Ilẹ̀ gbígbẹ sì máa di ìsun omi.+

Koríko tútù, esùsú àti òrépèté

Máa wà ní ibùgbé tí àwọn ajáko* ti ń sinmi.+

 8 Ọ̀nà kan sì máa wà níbẹ̀,+

Àní, ọ̀nà tí à ń pè ní Ọ̀nà Ìjẹ́mímọ́.

Aláìmọ́ kò ní gba ibẹ̀ kọjá.+

Àwọn tó ń rìn lójú ọ̀nà ló wà fún;

Òmùgọ̀ kankan ò sì ní rìn gbéregbère lọ síbẹ̀.

 9 Kò ní sí kìnnìún kankan níbẹ̀,

Ẹranko ẹhànnà kankan kò sì ní wá sórí rẹ̀.

A ò ní rí wọn níbẹ̀;+

Àwọn tí a tún rà nìkan ló máa gba ibẹ̀.+

10 Àwọn tí Jèhófà rà pa dà máa pa dà wá,+ wọ́n sì máa kígbe ayọ̀ wá sí Síónì.+

Ayọ̀ tí kò lópin máa dé orí wọn ládé.+

Wọ́n á máa yọ̀ gidigidi, inú wọn á sì máa dùn,

Ẹ̀dùn ọkàn àti ìbànújẹ́ kò ní sí mọ́.+

36 Ní ọdún kẹrìnlá Ọba Hẹsikáyà, Senakérúbù ọba Ásíríà+ wá gbéjà ko gbogbo ìlú olódi Júdà, ó sì gbà wọ́n.+ 2 Ọba Ásíríà wá rán Rábúṣákè*+ pẹ̀lú ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọmọ ogun láti Lákíṣì+ sí Ọba Hẹsikáyà ní Jerúsálẹ́mù. Wọ́n dúró síbi tí adágún omi tó wà lápá òkè ń gbà,+ èyí tó wà lójú ọ̀nà tó lọ sí pápá alágbàfọ̀.+ 3 Élíákímù+ ọmọ Hilikáyà, ẹni tó ń bójú tó agbo ilé* àti Ṣébínà+ akọ̀wé pẹ̀lú Jóà ọmọ Ásáfù akọ̀wé ìrántí sì jáde wá bá a.

4 Torí náà, Rábúṣákè sọ fún wọn pé: “Ẹ jọ̀ọ́, ẹ sọ fún Hẹsikáyà pé, ‘Ohun tí ọba ńlá, ọba Ásíríà sọ nìyí: “Kí lo gbọ́kàn lé?+ 5 Ò ń sọ pé, ‘Mo ní ọgbọ́n àti agbára láti jagun,’ àmọ́ ọ̀rọ̀ ẹnu lásán nìyẹn. Ta lo gbẹ́kẹ̀ lé, tí o fi gbójúgbóyà ṣọ̀tẹ̀ sí mi?+ 6 Wò ó! Ṣé Íjíbítì tó dà bí esùsú* fífọ́ yìí lo gbẹ́kẹ̀ lé, tó jẹ́ pé bí èèyàn bá fara tì í, ṣe ló máa wọ àtẹ́lẹwọ́ rẹ̀, tí á sì gún un yọ? Bí Fáráò ọba Íjíbítì ṣe rí nìyẹn sí gbogbo àwọn tó gbẹ́kẹ̀ lé e.+ 7 Tí ẹ bá sì sọ fún mi pé, ‘Jèhófà Ọlọ́run wa ni a gbẹ́kẹ̀ lé,’ ṣé òun kọ́ ni Hẹsikáyà mú àwọn ibi gíga rẹ̀ àti àwọn pẹpẹ rẹ̀ kúrò,+ tó sì sọ fún Júdà àti Jerúsálẹ́mù pé, ‘Iwájú pẹpẹ yìí ni kí ẹ ti máa forí balẹ̀’?”’+ 8 Ní báyìí, ẹ wò ó, olúwa mi ọba Ásíríà+ pè yín níjà: Ẹ jẹ́ kí n fún yín ní ẹgbẹ̀rún méjì (2,000) ẹṣin, ká wá wò ó bóyá ẹ máa lè rí àwọn agẹṣin tó máa gùn wọ́n. 9 Báwo wá ni ẹ ṣe lè borí gómìnà kan ṣoṣo tó kéré jù lára àwọn ìránṣẹ́ olúwa mi, nígbà tó jẹ́ pé Íjíbítì lẹ gbẹ́kẹ̀ lé pé ó máa fún yín ní àwọn kẹ̀kẹ́ ẹṣin àti àwọn agẹṣin? 10 Ṣé láìgba àṣẹ lọ́wọ́ Jèhófà ni mo wá gbéjà ko ilẹ̀ yìí láti pa á run ni? Jèhófà fúnra rẹ̀ sọ fún mi pé, ‘Lọ gbéjà ko ilẹ̀ yìí, kí o sì pa á run.’”

11 Ni Élíákímù àti Ṣébínà+ pẹ̀lú Jóà bá sọ fún Rábúṣákè+ pé: “Jọ̀ọ́, bá àwa ìránṣẹ́ rẹ sọ̀rọ̀ ní èdè Árámáíkì*+ torí a gbọ́ èdè náà; má fi èdè àwọn Júù bá wa sọ̀rọ̀ lójú àwọn èèyàn tó wà lórí ògiri.”+ 12 Ṣùgbọ́n Rábúṣákè sọ pé: “Ṣé ẹ̀yin àti olúwa yín nìkan ni olúwa mi ní kí n sọ ọ̀rọ̀ yìí fún ni? Ṣé kò tún rán mi sí àwọn ọkùnrin tó ń jókòó lórí ògiri, àwọn tó máa jẹ ìgbẹ́ ara wọn, tí wọ́n sì máa mu ìtọ̀ ara wọn pẹ̀lú yín?”

13 Rábúṣákè bá dìde, ó gbé ohùn rẹ̀ sókè, ó sì fi èdè àwọn Júù sọ̀rọ̀,+ ó ní: “Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ ọba ńlá, ọba Ásíríà.+ 14 Ohun tí ọba sọ nìyí, ‘Ẹ má ṣe jẹ́ kí Hẹsikáyà tàn yín jẹ, nítorí kò lè gbà yín sílẹ̀.+ 15 Ẹ má sì jẹ́ kí Hẹsikáyà mú kí ẹ gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà,+ bó ṣe ń sọ pé: “Ó dájú pé Jèhófà máa gbà wá, a ò sì ní fi ìlú yìí lé ọba Ásíríà lọ́wọ́.” 16 Ẹ má fetí sí Hẹsikáyà, torí ohun tí ọba Ásíríà sọ nìyí: “Ẹ bá mi ṣe àdéhùn àlàáfíà, kí ẹ sì túúbá,* kálukú yín á máa jẹ látinú àjàrà rẹ̀ àti igi ọ̀pọ̀tọ́ rẹ̀, á sì máa mu omi látinú kòtò omi rẹ̀, 17 títí màá fi wá kó yín lọ sí ilẹ̀ tó dà bí ilẹ̀ yín,+ ilẹ̀ ọkà àti ti wáìnì tuntun, ilẹ̀ oúnjẹ àti ti àwọn ọgbà àjàrà. 18 Ẹ má ṣe jẹ́ kí Hẹsikáyà ṣì yín lọ́nà bó ṣe ń sọ pé, ‘Jèhófà máa gbà wá.’ Ǹjẹ́ ìkankan lára ọlọ́run àwọn orílẹ̀-èdè ti gba ilẹ̀ wọn kúrò lọ́wọ́ ọba Ásíríà?+ 19 Ibo ni àwọn ọlọ́run Hámátì àti ti Áápádì+ wà? Ibo ni àwọn ọlọ́run Séfáfáímù+ wà? Ǹjẹ́ wọ́n gba Samáríà kúrò lọ́wọ́ mi?+ 20 Èwo nínú gbogbo ọlọ́run àwọn ilẹ̀ yìí ló ti gba ilẹ̀ wọn kúrò lọ́wọ́ mi, tí Jèhófà yóò fi gba Jerúsálẹ́mù kúrò lọ́wọ́ mi?”’”+

21 Àmọ́ wọ́n dákẹ́, wọn ò fún un lésì kankan, nítorí àṣẹ ọba ni pé, “Ẹ ò gbọ́dọ̀ dá a lóhùn.”+ 22 Ṣùgbọ́n Élíákímù ọmọ Hilikáyà, ẹni tó ń bójú tó agbo ilé* àti Ṣébínà+ akọ̀wé pẹ̀lú Jóà ọmọ Ásáfù akọ̀wé ìrántí wá sọ́dọ̀ Hẹsikáyà, pẹ̀lú ẹ̀wù yíya lọ́rùn wọn, wọ́n sì sọ àwọn ọ̀rọ̀ Rábúṣákè fún un.

37 Gbàrà tí Ọba Hẹsikáyà gbọ́ ọ̀rọ̀ náà, ó fa ẹ̀wù rẹ̀ ya, ó fi aṣọ ọ̀fọ̀* bora, ó sì lọ sínú ilé Jèhófà.+ 2 Lẹ́yìn náà, ó rán Élíákímù, ẹni tó ń bójú tó agbo ilé* àti Ṣébínà akọ̀wé pẹ̀lú àwọn àgbààgbà nínú àwọn àlùfáà, wọ́n fi aṣọ ọ̀fọ̀ bora, ó sì rán wọn sí wòlíì Àìsáyà,+ ọmọ Émọ́ọ̀sì. 3 Wọ́n sọ fún un pé: “Ohun tí Hẹsikáyà sọ nìyí, ‘Ọjọ́ òní jẹ́ ọjọ́ wàhálà àti ti ìbáwí* àti ti ìtìjú; nítorí a dà bí aboyún tó fẹ́ bímọ,* àmọ́ tí kò ní okun láti bí i.+ 4 Bóyá Jèhófà Ọlọ́run rẹ máa gbọ́ ọ̀rọ̀ Rábúṣákè tí olúwa rẹ̀ ọba Ásíríà rán láti pẹ̀gàn Ọlọ́run alààyè,+ tí á sì pè é wá jíhìn nítorí àwọn ọ̀rọ̀ tí Jèhófà Ọlọ́run rẹ ti gbọ́. Torí náà, gbàdúrà+ nítorí àṣẹ́kù tó yè bọ́ yìí.’”+

5 Nítorí náà, àwọn ìránṣẹ́ Ọba Hẹsikáyà lọ sọ́dọ̀ Àìsáyà,+ 6 Àìsáyà sì sọ fún wọn pé: “Ẹ sọ fún olúwa yín pé, ‘Ohun tí Jèhófà sọ nìyí: “Má bẹ̀rù+ nítorí àwọn ọ̀rọ̀ tí o gbọ́, àwọn ọ̀rọ̀ tí àwọn ẹmẹ̀wà* ọba Ásíríà+ fi pẹ̀gàn mi. 7 Wò ó, màá fi ohun kan sí i lọ́kàn,* ó máa gbọ́ ìròyìn kan, á sì pa dà sí ilẹ̀ rẹ̀;+ màá sì jẹ́ kí wọ́n fi idà pa á ní ilẹ̀ òun fúnra rẹ̀.”’”+

8 Lẹ́yìn tí Rábúṣákè gbọ́ pé ọba Ásíríà ti kúrò ní Lákíṣì, ó pa dà sọ́dọ̀ rẹ̀, ó sì rí i tó ń bá Líbínà jà.+ 9 Ọba wá gbọ́ tí wọ́n sọ nípa Tíhákà ọba Etiópíà pé: “Ó ti jáde láti wá bá ọ jà.” Nígbà tó gbọ́, ó tún rán àwọn òjíṣẹ́ sí Hẹsikáyà+ pé: 10 “Ẹ sọ fún Hẹsikáyà ọba Júdà pé, ‘Má ṣe jẹ́ kí Ọlọ́run rẹ tí o gbẹ́kẹ̀ lé tàn ọ́ jẹ pé: “A kò ní fi Jerúsálẹ́mù lé ọba Ásíríà lọ́wọ́.”+ 11 Wò ó! O ti gbọ́ ohun tí àwọn ọba Ásíríà ṣe sí gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè, bí wọ́n ṣe pa wọ́n run.+ Ṣé o rò pé ìwọ lè bọ́ lọ́wọ́ wa ni? 12 Ǹjẹ́ àwọn ọlọ́run àwọn orílẹ̀-èdè tí àwọn baba ńlá mi pa run gbà wọ́n?+ Ibo ni Gósánì, Háránì,+ Réséfù àti àwọn èèyàn Édẹ́nì tó wà ní Tẹli-ásárì wà? 13 Ibo ni ọba Hámátì, ọba Áápádì, ọba àwọn ìlú Séfáfáímù,+ ọba Hénà àti ọba Ífà wà?’”

14 Hẹsikáyà gba àwọn lẹ́tà náà lọ́wọ́ àwọn òjíṣẹ́ náà, ó sì kà wọ́n. Lẹ́yìn náà, Hẹsikáyà lọ sí ilé Jèhófà, ó sì tẹ́ wọn* síwájú Jèhófà.+ 15 Hẹsikáyà wá bẹ̀rẹ̀ sí í gbàdúrà sí Jèhófà,+ ó sọ pé: 16 “Ìwọ Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun,+ Ọlọ́run Ísírẹ́lì, tí o jókòó sórí ìtẹ́ lókè* àwọn kérúbù, ìwọ nìkan ni Ọlọ́run tòótọ́ lórí gbogbo ìjọba ayé. Ìwọ lo dá ọ̀run àti ayé. 17 Fetí sílẹ̀, Jèhófà, kí o sì gbọ́!+ La ojú rẹ, Jèhófà, kí o sì rí i!+ Kí o gbọ́ gbogbo ọ̀rọ̀ tí Senakérúbù fi ránṣẹ́ láti pẹ̀gàn Ọlọ́run alààyè.+ 18 Jèhófà, òótọ́ ni pé àwọn ọba Ásíríà ti pa gbogbo ilẹ̀ run,+ títí kan ilẹ̀ wọn. 19 Wọ́n sì ti ju àwọn ọlọ́run wọn sínú iná,+ nítorí wọn kì í ṣe ọlọ́run, iṣẹ́ ọwọ́ èèyàn ni wọ́n,+ wọ́n jẹ́ igi àti òkúta. Ìdí nìyẹn tí wọ́n fi lè pa wọ́n run. 20 Àmọ́ ní báyìí, ìwọ Jèhófà Ọlọ́run wa, gbà wá lọ́wọ́ rẹ̀, kí gbogbo ìjọba ayé lè mọ̀ pé ìwọ Jèhófà nìkan ṣoṣo ni Ọlọ́run.”+

21 Àìsáyà ọmọ Émọ́ọ̀sì wá ránṣẹ́ sí Hẹsikáyà pé: “Ohun tí Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì sọ nìyí, ‘Torí pé o gbàdúrà sí mi nítorí Senakérúbù ọba Ásíríà,+ 22 ọ̀rọ̀ tí Jèhófà sọ nípa rẹ̀ nìyí:

“Wúńdíá ọmọbìnrin Síónì pẹ̀gàn rẹ, ó ti fi ọ́ ṣẹ̀sín.

Ọmọbìnrin Jerúsálẹ́mù mi orí rẹ̀ sí ọ.

23 Ta lo pẹ̀gàn,+ tí o sì sọ̀rọ̀ òdì sí?

Ta lo gbé ohùn rẹ sókè sí,+

Tí o sì gbé ojú rẹ ga sí?

Ẹni Mímọ́ Ísírẹ́lì mà ni!+

24 O tipasẹ̀ àwọn ìránṣẹ́ rẹ pẹ̀gàn Jèhófà,+ o sọ pé,

‘Pẹ̀lú ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn kẹ̀kẹ́ ogun mi,

Màá gun ibi gíga àwọn òkè,+

Ibi tó jìnnà jù lọ ní Lẹ́bánónì.

Ṣe ni màá gé àwọn igi kédárì rẹ̀ tó ga fíofío lulẹ̀, àwọn ààyò igi júnípà rẹ̀.

Màá wọ ibi tó ga jù tó máa ń sá sí, igbó kìjikìji rẹ̀.

25 Màá gbẹ́ kànga, màá sì mu omi;

Màá fi àtẹ́lẹsẹ̀ mi mú kí àwọn odò* Íjíbítì gbẹ.’

26 Ṣé o ò tíì gbọ́ ni? Tipẹ́tipẹ́ ni mo ti pinnu rẹ̀.*

Láti ọ̀pọ̀ ọjọ́ sẹ́yìn ni mo ti ṣètò rẹ̀.*+

Ní báyìí, màá ṣe é.+

Wàá sọ àwọn ìlú olódi di àwókù.+

27 Àwọn tó ń gbé inú wọn á di aláìlágbára;

Jìnnìjìnnì á bá wọn, ojú á sì tì wọ́n.

Wọ́n á rọ bí ewéko pápá àti bí koríko tútù ṣe máa ń rọ,

Bíi koríko orí òrùlé tí atẹ́gùn ìlà oòrùn ti jó gbẹ.

28 Àmọ́, mo mọ ìgbà tí o bá jókòó, ìgbà tí o bá jáde àti ìgbà tí o bá wọlé+

Àti ìgbà tí inú rẹ bá ru sí mi,+

29 Torí bí inú rẹ ṣe ń ru sí mi+ àti bí o ṣe ń ké ramúramù ti dé etí mi.+

Torí náà, màá fi ìwọ̀ mi kọ́ imú rẹ, màá fi ìjánu+ mi sáàárín ètè rẹ,

Ọ̀nà tí o gbà wá ni màá sì mú ọ gbà pa dà.”

30 “‘Ohun tó máa jẹ́ àmì fún ọ* nìyí: Lọ́dún yìí, ẹ ó jẹ ohun tó lalẹ̀ hù;* ní ọdún kejì, ọkà tó hù látinú ìyẹn ni ẹ ó jẹ; àmọ́ ní ọdún kẹta, ẹ ó fúnrúgbìn, ẹ ó sì kórè, ẹ ó gbin àwọn ọgbà àjàrà, ẹ ó sì jẹ èso wọn.+ 31 Ìyókù àwọn ará ilé Júdà tó sá àsálà+ máa ta gbòǹgbò nísàlẹ̀, wọ́n á sì so èso lókè. 32 Nítorí àṣẹ́kù kan máa jáde wá láti Jerúsálẹ́mù, àwọn tó là á já sì máa jáde wá láti Òkè Síónì.+ Ìtara Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun máa ṣe èyí.+

33 “‘Torí náà, ohun tí Jèhófà sọ nípa ọba Ásíríà+ nìyí:

“Kò ní wọ inú ìlú yìí,+

Bẹ́ẹ̀ ni kò ní ta ọfà sí ibẹ̀,

Tàbí kó fi apata dojú kọ ọ́,

Bẹ́ẹ̀ sì ni kò ní mọ òkìtì láti dó tì í.”’+

34 ‘Ọ̀nà tó gbà wá ló máa gbà pa dà;

Kò ní wọ inú ìlú yìí,’ ni Jèhófà wí.

35 ‘Màá gbèjà ìlú yìí,+ màá sì gbà á sílẹ̀ nítorí orúkọ mi+

Àti nítorí Dáfídì ìránṣẹ́ mi.’”+

36 Áńgẹ́lì Jèhófà wá jáde lọ, ó sì pa ọ̀kẹ́ mẹ́sàn-án ó lé ẹgbẹ̀rún márùn-ún (185,000) ọkùnrin nínú ibùdó àwọn ará Ásíríà. Nígbà tí àwọn èèyàn jí láàárọ̀ kùtù, wọ́n rí òkú nílẹ̀ bẹẹrẹbẹ.+ 37 Torí náà, Senakérúbù ọba Ásíríà kúrò níbẹ̀, ó pa dà sí Nínéfè,+ ó sì ń gbé ibẹ̀.+ 38 Bó ṣe ń forí balẹ̀ ní ilé* Nísírọ́kì ọlọ́run rẹ̀, àwọn ọmọ rẹ̀, Adiramélékì àti Ṣárésà fi idà pa á,+ wọ́n sì sá lọ sí ilẹ̀ Árárátì.+ Esari-hádónì+ ọmọ rẹ̀ sì jọba ní ipò rẹ̀.

38 Ní àkókò náà, Hẹsikáyà ṣàìsàn dé ojú ikú.+ Wòlíì Àìsáyà+ ọmọ Émọ́ọ̀sì wá bá a, ó sì sọ fún un pé, “Ohun tí Jèhófà sọ nìyí: ‘Sọ ohun tí agbo ilé rẹ máa ṣe fún wọn, torí pé o máa kú; o ò ní yè é.’”+ 2 Ni Hẹsikáyà bá yíjú sí ògiri, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í gbàdúrà sí Jèhófà, ó ní: 3 “Mo bẹ̀ ọ́, Jèhófà, jọ̀ọ́ rántí+ bí mo ṣe fi òtítọ́ àti gbogbo ọkàn mi rìn níwájú rẹ,+ ohun tó dáa ní ojú rẹ sì ni mo ṣe.” Hẹsikáyà sì bẹ̀rẹ̀ sí í sunkún pẹ̀rẹ̀pẹ̀rẹ̀.

4 Jèhófà wá sọ fún Àìsáyà pé: 5 “Pa dà lọ sọ fún Hẹsikáyà pé,+ ‘Ohun tí Jèhófà Ọlọ́run Dáfídì baba ńlá rẹ sọ nìyí: “Mo ti gbọ́ àdúrà rẹ.+ Mo ti rí omijé rẹ.+ Wò ó, màá fi ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún (15) kún ọjọ́ ayé* rẹ,+ 6 màá gba ìwọ àti ìlú yìí lọ́wọ́ ọba Ásíríà, màá sì gbèjà ìlú yìí.+ 7 Àmì tí Jèhófà fún ọ nìyí láti mú un dá ọ lójú pé Jèhófà máa mú ọ̀rọ̀ tó sọ ṣẹ:+ 8 Màá mú kí òjìji oòrùn tó ń sọ̀ kalẹ̀ lórí àtẹ̀gùn* Áhásì pa dà sẹ́yìn ní ìgbésẹ̀ mẹ́wàá.”’”+ Oòrùn wá pa dà sẹ́yìn ní ìgbésẹ̀ mẹ́wàá lẹ́yìn tó ti kọ́kọ́ lọ síwájú lórí àtẹ̀gùn náà.

9 Ìwé* tí Hẹsikáyà ọba Júdà kọ nígbà tó ń ṣàìsàn, tí ara rẹ̀ sì yá.

10 Mo sọ pé: “Ní àárín ọjọ́ ayé mi,

Mo gbọ́dọ̀ wọnú àwọn ẹnubodè Isà Òkú.*

A máa fi àwọn ọdún mi tó kù dù mí.”

11 Mo sọ pé: “Mi ò ní rí Jáà,* àní Jáà ní ilẹ̀ alààyè.+

Mi ò ní wo aráyé mọ́,

Tí mo bá wà lọ́dọ̀ àwọn tó ń gbé ibi tí gbogbo nǹkan ti dáwọ́ dúró.

12 A ti fa ibùgbé mi tu, a sì ti mú un kúrò lọ́dọ̀ mi+

Bí àgọ́ olùṣọ́ àgùntàn.

Mo ti ká ẹ̀mí mi bíi ti ẹni tó ń hun aṣọ;

Ó gé mi kúrò bí àwọn òwú tó wà lóròó.

Ò ń mú mi wá sí òpin+ láti ojúmọmọ títí di òru.

13 Mo fira mi lọ́kàn balẹ̀ títí di àárọ̀.

Ó ń fọ́ gbogbo egungun mi bíi kìnnìún;

Ò ń mú mi wá sí òpin+ láti ojúmọmọ títí di òru.

14 Mò ń ké ṣíoṣío bí ẹyẹ olófèéèré àti ẹ̀gà;*+

Mò ń ké kúùkúù bí àdàbà.+

Ojú mi ń wo ibi gíga títí ó fi rẹ̀ mí:+

‘Jèhófà, ìdààmú ti bò mí mọ́lẹ̀;

Ràn mí lọ́wọ́!’*+

15 Kí ni kí n sọ?

Ó ti bá mi sọ̀rọ̀, ó sì ti ṣe nǹkan kan.

Màá máa rìn tìrẹ̀lẹ̀tìrẹ̀lẹ̀* ní gbogbo ọdún mi

Torí ẹ̀dùn ọkàn tó bá mi.*

16 ‘Jèhófà, àwọn nǹkan yìí* ló ń mú gbogbo èèyàn wà láàyè,

Ìwàláàyè ẹ̀mí mi sì wà nínú wọn.

O máa mú kí n pa dà ní ìlera tó dáa, o sì máa dá ẹ̀mí mi sí.+

17 Wò ó! Dípò àlàáfíà, ìbànújẹ́ ńlá ló bá mi;

Àmọ́ torí ìfẹ́ tí o ní sí mi,*

O pa mí mọ́ kúrò nínú kòtò ìparun.+

O ti ju gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ mi sí ẹ̀yìn rẹ.*+

18 Torí pé Isà Òkú* ò lè yìn ọ́ lógo,+

Ikú ò lè yìn ọ́.+

Àwọn tó lọ sínú kòtò kò lè retí ìṣòtítọ́ rẹ.+

19 Alààyè, àní alààyè lè yìn ọ́,

Bí mo ṣe lè yìn ọ́ lónìí.

Bàbá lè kọ́ àwọn ọmọ rẹ̀ nípa ìṣòtítọ́ rẹ.+

20 Jèhófà, gbà mí,

A sì máa fi àwọn ohun ìkọrin olókùn tín-ín-rín kọ àwọn orin mi+

Ní gbogbo ọjọ́ ayé wa ní ilé Jèhófà.’”+

21 Àìsáyà wá sọ pé: “Ẹ mú ìṣù ọ̀pọ̀tọ́ gbígbẹ wá, kí ẹ sì fi sí eéwo náà, kí ara rẹ̀ lè yá.”+ 22 Hẹsikáyà ti béèrè pé: “Àmì wo ni màá fi mọ̀ pé màá lọ sí ilé Jèhófà?”+

39 Ní àkókò yẹn, ọba Bábílónì, ìyẹn Merodaki-báládánì ọmọ Báládánì, fi àwọn lẹ́tà àti ẹ̀bùn ránṣẹ́ sí Hẹsikáyà,+ torí ó gbọ́ pé Hẹsikáyà ṣàìsàn, ara rẹ̀ sì ti yá.+ 2 Hẹsikáyà kí wọn káàbọ̀ tayọ̀tayọ̀,* ó sì fi ohun tó wà nínú ilé ìṣúra rẹ̀ hàn wọ́n,+ ìyẹn fàdákà, wúrà, òróró básámù àti àwọn òróró míì tó ṣeyebíye, pẹ̀lú gbogbo ilé tó ń kó ohun ìjà sí àti gbogbo ohun tó wà nínú àwọn ibi ìṣúra rẹ̀. Kò sí nǹkan tí Hẹsikáyà kò fi hàn wọ́n nínú ilé* rẹ̀ àti ní gbogbo agbègbè tó wà lábẹ́ àkóso rẹ̀.

3 Lẹ́yìn náà, wòlíì Àìsáyà wá sọ́dọ̀ Ọba Hẹsikáyà, ó sì béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé: “Kí ni àwọn ọkùnrin yìí sọ, ibo ni wọ́n sì ti wá?” Torí náà, Hẹsikáyà sọ pé: “Ibi tó jìnnà ni wọ́n ti wá, láti Bábílónì.”+ 4 Ó tún béèrè pé: “Kí ni wọ́n rí nínú ilé* rẹ?” Hẹsikáyà fèsì pé: “Gbogbo ohun tó wà nínú ilé* mi ni wọ́n rí. Kò sí nǹkan kan tó wà nínú àwọn ibi ìṣúra mi tí mi ò fi hàn wọ́n.”

5 Àìsáyà wá sọ fún Hẹsikáyà pé: “Gbọ́ ọ̀rọ̀ Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun, 6 ‘Wò ó! Ọjọ́ ń bọ̀ tí wọ́n máa kó gbogbo ohun tó wà nínú ilé* rẹ àti gbogbo ohun tí àwọn baba ńlá rẹ ti kó jọ títí di òní yìí lọ sí Bábílónì. Kò ní ku nǹkan kan,’+ ni Jèhófà wí.+ 7 ‘Wọ́n á mú àwọn kan lára àwọn ọmọ tí o máa bí, wọ́n á sì di òṣìṣẹ́ ààfin ní ààfin ọba Bábílónì.’”+

8 Ni Hẹsikáyà bá sọ fún Àìsáyà pé: “Ọ̀rọ̀ Jèhófà tí o sọ dáa.” Ó wá fi kún un pé: “Torí àlàáfíà àti ìfọkànbalẹ̀* máa wà lásìkò* tèmi.”+

40 “Ẹ tu àwọn èèyàn mi nínú, ẹ tù wọ́n nínú,” ni Ọlọ́run yín wí.+

 2 “Ẹ sọ ọ̀rọ̀ tó máa wọ Jerúsálẹ́mù lọ́kàn,*

Kí ẹ sì kéde fún un pé iṣẹ́ rẹ̀ tó pọn dandan ti parí,

Pé a ti san gbèsè ẹ̀bi tó jẹ.+

Ó ti gba ohun tó kún rẹ́rẹ́* lọ́wọ́ Jèhófà fún gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀.”+

 3 Ohùn ẹnì kan ń ké nínú aginjù pé:

“Ẹ tún ọ̀nà Jèhófà ṣe!*+

Ẹ la ọ̀nà tó tọ́  + gba inú aṣálẹ̀ fún Ọlọ́run wa.+

 4 Kí ẹ mú kí gbogbo àfonífojì ga sókè,

Kí ẹ sì mú kí gbogbo òkè ńlá àti òkè kéékèèké wálẹ̀.

Kí ilẹ̀ tó rí gbágungbàgun di ilẹ̀ tó tẹ́jú,

Kí ilẹ̀ kángunkàngun sì di pẹ̀tẹ́lẹ̀.+

 5 A máa ṣí ògo Jèhófà payá,+

Gbogbo ẹran ara* sì jọ máa rí i,+

Torí Jèhófà ti fi ẹnu ara rẹ̀ sọ ọ́.”

 6 Fetí sílẹ̀! Ẹnì kan ń sọ pé: “Ké jáde!”

Ẹlòmíì béèrè pé: “Igbe kí ni kí n ké?”

“Koríko tútù ni gbogbo ẹran ara.*

Gbogbo ìfẹ́ wọn tí kì í yẹ̀ dà bí ìtànná àwọn ewéko.+

 7 Koríko tútù máa ń gbẹ dà nù,

Ìtànná máa ń rọ,+

Torí pé èémí* Jèhófà fẹ́ lù ú.+

Ó dájú pé koríko tútù ni àwọn èèyàn náà.

 8 Koríko tútù máa ń gbẹ dà nù,

Ìtànná máa ń rọ,

Ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ Ọlọ́run wa máa wà títí láé.”+

 9 Lọ sórí òkè tó ga,

Ìwọ obìnrin tó ń mú ìròyìn ayọ̀ wá fún Síónì.+

Gbé ohùn rẹ sókè tagbáratagbára,

Ìwọ obìnrin tó ń mú ìròyìn ayọ̀ wá fún Jerúsálẹ́mù.

Gbé e sókè, má bẹ̀rù.

Kéde fún àwọn ìlú Júdà pé: “Ọlọ́run yín rèé.”+

10 Wò ó! Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ máa wá tagbáratagbára,

Apá rẹ̀ sì máa bá a ṣàkóso.+

Wò ó! Èrè rẹ̀ wà pẹ̀lú rẹ̀,

Ẹ̀san rẹ̀ sì wà níwájú rẹ̀.+

11 Ó máa bójú tó* agbo ẹran rẹ̀ bíi ti olùṣọ́ àgùntàn.+

Ó máa fi apá rẹ̀ kó àwọn ọ̀dọ́ àgùntàn jọ,

Ó sì máa gbé wọn sí àyà rẹ̀.

Ó máa rọra da àwọn tó ń fọ́mọ lọ́mú.+

12 Ta ló ti fi àtẹ́lẹwọ́ rẹ̀ wọn omi,+

Tó sì ti fi ìbú àtẹ́lẹwọ́* rẹ̀ wọn* ọ̀run?

Ta ló ti kó gbogbo erùpẹ̀ ilẹ̀ sínú òṣùwọ̀n,+

Tàbí tó ti wọn àwọn òkè ńlá lórí ìwọ̀n,

Tó sì ti wọn àwọn òkè kéékèèké lórí òṣùwọ̀n?

13 Ta ló ti díwọ̀n* ẹ̀mí Jèhófà,

Ta ló sì lè dá a lẹ́kọ̀ọ́ gẹ́gẹ́ bí agbani-nímọ̀ràn rẹ̀?+

14 Ta ló ti bá fikùn lukùn kó lè ní òye,

Tàbí ta ló kọ́ ọ ní ọ̀nà ìdájọ́ òdodo,

Tó kọ́ ọ ní ìmọ̀,

Tàbí tó fi ọ̀nà òye tòótọ́ hàn án?+

15 Wò ó! Àwọn orílẹ̀-èdè dà bí ẹ̀kán omi kan látinú korobá,

A sì kà wọ́n sí eruku fẹ́ẹ́rẹ́fẹ́ lórí òṣùwọ̀n.+

Wò ó! Ó ń gbé àwọn erékùṣù sókè bí eruku lẹ́búlẹ́bú.

16 Lẹ́bánónì pàápàá kò tó láti mú kí iná máa jó,*

Àwọn ẹran igbó rẹ̀ kò sì tó fún ẹbọ sísun.

17 Gbogbo orílẹ̀-èdè dà bí ohun tí kò sí ní iwájú rẹ̀;+

Ó kà wọ́n sí ohun tí kò já mọ́ nǹkan kan, bí ohun tí kò sí rárá.+

18 Ta ni ẹ lè fi Ọlọ́run wé?+

Kí lẹ lè fi sẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀ tó máa jọ ọ́?+

19 Oníṣẹ́ ọnà ṣe ère,*

Oníṣẹ́ irin fi wúrà bò ó,+

Ó sì fi fàdákà rọ ẹ̀wọ̀n.

20 Ó mú igi láti fi ṣe ọrẹ,+

Igi tí kò ní jẹrà.

Ó wá oníṣẹ́ ọnà tó já fáfá,

Láti ṣe ère gbígbẹ́ tí kò ní ṣubú.+

21 Ṣé ẹ kò mọ̀ ni?

Ṣé ẹ kò tíì gbọ́ ni?

Ṣé wọn ò sọ fún yín láti ìbẹ̀rẹ̀ ni?

Ṣé kò yé yín látìgbà tí a ti dá ayé?+

22 Ẹnì kan wà tó ń gbé orí òbìrìkìtì* ayé,+

Àwọn tó ń gbé inú rẹ̀ sì dà bíi tata,

Ó ń na ọ̀run bí aṣọ fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ tó ní ihò wínníwínní,

Ó sì tẹ́ ẹ bí àgọ́ láti máa gbé.+

23 Ó ń sọ àwọn aláṣẹ di ẹni tí kò já mọ́ nǹkan kan,

Ó sì ń sọ àwọn adájọ́* ayé di ohun tí kò sí rárá.

24 Bóyá la gbìn wọ́n rí,

Bóyá la fúnrúgbìn wọn rí,

Bóyá ni kùkùté wọn ta gbòǹgbò rí nínú ilẹ̀,

A fẹ́ atẹ́gùn lù wọ́n, wọ́n sì gbẹ dà nù,

Afẹ́fẹ́ gbé wọn lọ bí àgékù pòròpórò.+

25 “Ta lẹ lè fi mí wé bóyá mo bá a dọ́gba?” ni Ẹni Mímọ́ wí.

26 “Ẹ gbé ojú yín sókè ọ̀run, kí ẹ sì wò ó.

Ta ló dá àwọn nǹkan yìí?+

Òun ni Ẹni tó ń mú wọn jáde bí ẹgbẹ́ ọmọ ogun ní iye-iye;

Ó ń fi orúkọ pe gbogbo wọn.+

Torí okun rẹ̀ tó fi ń ṣiṣẹ́ pọ̀ yanturu, agbára rẹ̀ sì ń bani lẹ́rù,+

Ìkankan nínú wọn ò di àwátì.

27 Ìwọ Jékọ́bù, kí ló dé tí o fi sọ báyìí, àti ìwọ Ísírẹ́lì, kí ló dé tí o fi kéde pé,

‘Jèhófà ò rí ọ̀nà mi,

Mi ò sì rí ìdájọ́ òdodo gbà lọ́dọ̀ Ọlọ́run’?+

28 Ṣé o ò mọ̀ ni? Ṣé o ò tíì gbọ́ ni?

Jèhófà, Ẹlẹ́dàá àwọn ìkángun ayé, jẹ́ Ọlọ́run títí ayé.+

Kì í rẹ̀ ẹ́, okun rẹ̀ kì í sì í tán.+

Àwámáridìí ni òye rẹ̀.*+

29 Ó ń fún ẹni tó ti rẹ̀ ní agbára,

Ó sì ń fún àwọn tí kò lókun* ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ okun.+

30 Ó máa rẹ àwọn ọmọdékùnrin, okun wọn sì máa tán,

Àwọn ọ̀dọ́kùnrin máa kọsẹ̀, wọ́n á sì ṣubú,

31 Àmọ́ àwọn tó gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà máa jèrè okun pa dà.

Wọ́n máa fi ìyẹ́ fò lọ sókè réré bí ẹyẹ idì.+

Wọ́n máa sáré, okun ò ní tán nínú wọn;

Wọ́n máa rìn, kò sì ní rẹ̀ wọ́n.”+

41 “Ẹ dákẹ́, kí ẹ sì fetí sí mi,* ẹ̀yin erékùṣù;

Kí àwọn orílẹ̀-èdè pa dà ní agbára.

Kí wọ́n sún mọ́ tòsí; kí wọ́n wá sọ̀rọ̀.+

Ẹ jẹ́ ká kóra jọ fún ìdájọ́.

 2 Ta ló ti gbé ẹnì kan dìde láti ibi tí oòrùn ti ń yọ,*+

Tó pè é nínú òdodo wá síbi ẹsẹ̀ Rẹ̀,*

Láti fa àwọn orílẹ̀-èdè lé e lọ́wọ́,

Kó sì mú kó tẹ àwọn ọba lórí ba?+

Ta ló ń sọ wọ́n di eruku níwájú idà rẹ̀,

Bí àgékù pòròpórò tí atẹ́gùn ń gbé kiri níwájú ọfà rẹ̀?

 3 Ó ń lé wọn, ohunkóhun ò sì dí i lọ́wọ́

Lójú ọ̀nà tí kò fẹsẹ̀ tẹ̀ rí.

 4 Ta ló ṣe èyí? Iṣẹ́ ọwọ́ ta sì ni,

Tó ń pe àwọn ìran láti ìbẹ̀rẹ̀?

Èmi Jèhófà, ni Ẹni Àkọ́kọ́;+

Èmi kan náà ni mo sì wà pẹ̀lú àwọn tó kẹ́yìn.”+

 5 Àwọn erékùṣù rí i, ẹ̀rù sì bà wọ́n.

Àwọn ìkángun ayé bẹ̀rẹ̀ sí í wárìrì.

Wọ́n sún mọ́ tòsí, wọ́n sì bọ́ síwájú.

 6 Kálukú ń ran ẹnì kejì rẹ̀ lọ́wọ́,

Wọ́n ń sọ fún àwọn arákùnrin wọn pé: “Ẹ jẹ́ alágbára.”

 7 Torí náà, oníṣẹ́ ọnà ń fún oníṣẹ́ irin+ lókun;

Ẹni tó ń fi òòlù irin* lu nǹkan di pẹlẹbẹ

Ń fún ẹni tó ń fi òòlù lu nǹkan lórí irin lókun.

Ó ń sọ nípa ohun tí wọ́n jó pọ̀ pé: “Ó dáa.”

Wọ́n wá fi ìṣó kàn án, kó má bàa ṣubú.

 8 “Àmọ́ ìwọ Ísírẹ́lì ni ìránṣẹ́ mi,+

Ìwọ Jékọ́bù, ẹni tí mo yàn,+

Ọmọ* Ábúráhámù ọ̀rẹ́ mi,+

 9 Ìwọ tí mo mú láti àwọn ìkángun ayé,+

Ìwọ tí mo pè láti àwọn apá ibi tó jìnnà jù níbẹ̀.

Mo sọ fún ọ pé, ‘Ìwọ ni ìránṣẹ́ mi;+

Mo ti yàn ọ́; Mi ò kọ̀ ọ́.+

10 Má bẹ̀rù, torí mo wà pẹ̀lú rẹ.+

Má ṣàníyàn, torí èmi ni Ọlọ́run rẹ.+

Màá fún ọ lókun, àní, màá ràn ọ́ lọ́wọ́,+

Ní tòótọ́, màá fi ọwọ́ ọ̀tún òdodo mi dì ọ́ mú ṣinṣin.’

11 Wò ó! Ojú máa ti gbogbo àwọn tó ń bínú sí ọ, wọ́n sì máa tẹ́.+

Àwọn tó ń bá ọ jà máa di ẹni tí kò já mọ́ nǹkan kan, wọ́n sì máa ṣègbé.+

12 O máa wá àwọn tó ń bá ọ jà, àmọ́ o ò ní rí wọn;

Àwọn tó ń bá ọ jagun máa dà bí ohun tí kò sí, bí ohun tí kò sí rárá.+

13 Torí pé èmi Jèhófà Ọlọ́run rẹ ń di ọwọ́ ọ̀tún rẹ mú,

Ẹni tó ń sọ fún ọ pé, ‘Má bẹ̀rù. Màá ràn ọ́ lọ́wọ́.’+

14 Má bẹ̀rù, ìwọ Jékọ́bù kòkòrò mùkúlú,*+

Ẹ̀yin ọkùnrin Ísírẹ́lì, màá ràn yín lọ́wọ́,” ni Jèhófà, Olùtúnrà yín,+ Ẹni Mímọ́ Ísírẹ́lì wí.

15 “Wò ó! Mo ti sọ ọ́ di ohun tí wọ́n fi ń pakà,+

Ohun tuntun tó ní eyín olójú méjì tí wọ́n fi ń pakà.

O máa tẹ àwọn òkè ńlá mọ́lẹ̀, o máa fọ́ wọn túútúú,

O sì máa ṣe àwọn òkè kéékèèké bí ìyàngbò.*

16 O máa fẹ́ wọn bí ọkà,

Atẹ́gùn sì máa gbé wọn lọ;

Ìjì máa tú wọn ká.

Inú rẹ máa dùn torí Jèhófà,+

O sì máa fi Ẹni Mímọ́ Ísírẹ́lì yangàn.”+

17 “Àwọn aláìní àti àwọn tálákà ń wá omi, àmọ́ kò sí rárá.

Òùngbẹ ti mú kí ahọ́n wọn gbẹ.+

Èmi Jèhófà máa dá wọn lóhùn.+

Èmi Ọlọ́run Ísírẹ́lì ò ní fi wọ́n sílẹ̀.+

18 Màá mú kí odò ṣàn lórí àwọn òkè tí nǹkan ò hù sí,+

Màá sì mú kí omi sun ní àwọn pẹ̀tẹ́lẹ̀.+

Màá sọ aginjù di adágún omi tí esùsú* kún inú rẹ̀,

Màá sì sọ ilẹ̀ tí kò lómi di orísun omi.  +

19 Màá gbin igi kédárì sínú aṣálẹ̀,

Màá gbin igi bọn-ọ̀n-ní, igi mátílì àti igi ahóyaya síbẹ̀.+

Màá gbin igi júnípà sí aṣálẹ̀ tó tẹ́jú,

Pẹ̀lú igi áàṣì àti igi sípírẹ́sì,+

20 Kí gbogbo èèyàn lè rí i, kí wọ́n sì mọ̀,

Kí wọ́n fiyè sí i, kó sì yé wọn,

Pé ọwọ́ Jèhófà ló ṣe èyí,

Ẹni Mímọ́ Ísírẹ́lì ló sì dá a.”+

21 “Ẹ ro ẹjọ́ yín,” ni Jèhófà wí.

“Ẹ gbèjà ara yín,” ni Ọba Jékọ́bù wí.

22 “Ẹ mú ẹ̀rí wá, kí ẹ sì sọ ohun tó máa ṣẹlẹ̀ fún wa.

Ẹ sọ àwọn ohun àtijọ́* fún wa,

Ká lè ronú nípa wọn,* ká sì mọ ibi tí wọ́n máa já sí.

Tàbí kí ẹ kéde àwọn ohun tó ń bọ̀ fún wa.+

23 Ẹ sọ àwọn ohun tó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú fún wa,

Ká lè mọ̀ pé ọlọ́run ni yín.+

Àní, ẹ ṣe nǹkan kan, ì báà jẹ́ rere tàbí búburú,

Kó lè yà wá lẹ́nu tí a bá rí i.+

24 Ẹ wò ó! Ohun tí kò sí ni yín,

Iṣẹ́ ọwọ́ yín kò sì já mọ́ nǹkan kan.+

Ohun ìríra ni ẹnikẹ́ni tó bá yàn yín.+

25 Mo ti gbé ẹnì kan dìde láti àríwá, ó sì máa wá,+

Ẹnì kan láti ibi tí oòrùn ti ń yọ*+ tó máa ké pe orúkọ mi.

Ó máa tẹ àwọn alákòóso* mọ́lẹ̀ bíi pé amọ̀ ni wọ́n,+

Bí amọ̀kòkò tó ń tẹ amọ̀ rírin mọ́lẹ̀.

26 Ta ló sọ èyí láti ìbẹ̀rẹ̀, ká lè mọ̀,

Tàbí láti ìgbà àtijọ́, ká lè sọ pé, ‘Ó tọ̀nà’?+

Lóòótọ́, kò sí ẹni tó sọ ọ́!

Kò sí ẹni tó kéde rẹ̀!

Kò sí ẹni tó gbọ́ ohunkóhun látọ̀dọ̀ rẹ!”+

27 Èmi ni mo kọ́kọ́ sọ fún Síónì pé: “Wò ó! Àwọn nìyí!”+

Màá sì rán ẹni tó ń mú ìròyìn ayọ̀ wá sí Jerúsálẹ́mù.+

28 Àmọ́ mò ń wò, kò sì sí ẹnì kankan;

Kò sí ìkankan nínú wọn tó ń gbani nímọ̀ràn.

Mo sì ń sọ fún wọn ṣáá pé kí wọ́n fèsì.

29 Wò ó! Gbogbo wọn jẹ́ ẹ̀tàn.*

Iṣẹ́ wọn kò já mọ́ nǹkan kan.

Afẹ́fẹ́ lásán àti ohun tí kò sí rárá ni àwọn ère onírin* wọn.+

42 Wò ó! Ìránṣẹ́ mi,+ tí mò ń tì lẹ́yìn!

Àyànfẹ́ mi,+ ẹni tí mo* tẹ́wọ́ gbà!+

Mo ti fi ẹ̀mí mi sínú rẹ̀;+

Ó máa mú ìdájọ́ òdodo wá fún àwọn orílẹ̀-èdè.+

 2 Kò ní ké jáde tàbí kó gbé ohùn rẹ̀ sókè,

Kò sì ní jẹ́ ká gbọ́ ohùn rẹ̀ lójú ọ̀nà.+

 3 Kò ní ṣẹ́ esùsú* kankan tó ti fọ́,

Kò sì ní pa òwú àtùpà kankan tó ń jó lọ́úlọ́ú tí wọ́n fi ọ̀gbọ̀ ṣe.+

Ó máa fi òótọ́ ṣe ìdájọ́ òdodo.+

 4 Kò ní rẹ̀ ẹ́, a ò sì ní tẹ̀ ẹ́ rẹ́ títí ó fi máa fìdí ìdájọ́ òdodo múlẹ̀ ní ayé;+

Àwọn erékùṣù sì ń dúró de òfin* rẹ̀.

 5 Ohun tí Jèhófà, Ọlọ́run tòótọ́, sọ nìyí,

Ẹlẹ́dàá ọ̀run àti Atóbilọ́lá tó nà án jáde,+

Ẹni tó tẹ́ ayé àti èso rẹ̀,+

Ẹni tó fún àwọn èèyàn inú rẹ̀ ní èémí,+

Tó sì fún àwọn tó ń rìn lórí rẹ̀ ní ẹ̀mí:+

 6 “Èmi Jèhófà, ti pè ọ́ nínú òdodo;

Mo ti di ọwọ́ rẹ mú.

Màá dáàbò bò ọ́, màá sì fi ọ́ ṣe májẹ̀mú fún àwọn èèyàn náà+

Àti bí ìmọ́lẹ̀ àwọn orílẹ̀-èdè,+

 7 Kí o lè la àwọn ojú tó fọ́,+

Láti mú ẹlẹ́wọ̀n jáde kúrò nínú àjà ilẹ̀

Àti àwọn tó jókòó sínú òkùnkùn jáde kúrò ní ẹ̀wọ̀n.+

 8 Èmi ni Jèhófà. Orúkọ mi nìyẹn;

Èmi kì í fi ògo mi fún ẹlòmíì,*

Èmi kì í sì í fi ìyìn mi fún àwọn ère gbígbẹ́.+

 9 Wò ó, àwọn nǹkan àkọ́kọ́ ti ṣẹlẹ̀;

Ní báyìí, mò ń kéde àwọn nǹkan tuntun.

Kí wọ́n tó rú yọ, mo sọ fún yín nípa wọn.”+

10 Ẹ kọ orin tuntun sí Jèhófà,+

Ẹ yìn ín láti àwọn ìkángun ayé,+

Ẹ̀yin tí ẹ̀ ń lọ sínú òkun àti gbogbo ohun tó kún inú rẹ̀,

Ẹ̀yin erékùṣù àti àwọn tó ń gbé inú wọn.+

11 Kí aginjù àti àwọn ìlú rẹ̀ gbé ohùn wọn sókè,+

Àwọn ìgbèríko tí Kídárì+ ń gbé.

Kí àwọn tó ń gbé níbi àpáta kígbe ayọ̀;

Kí wọ́n ké jáde láti orí àwọn òkè.

12 Kí wọ́n gbé ògo fún Jèhófà,

Kí wọ́n sì kéde ìyìn rẹ̀ ní àwọn erékùṣù.+

13 Jèhófà máa jáde lọ bí akíkanjú ọkùnrin.+

Ó máa mú kí ìtara rẹ̀ sọjí bíi ti jagunjagun.+

Ó máa kígbe, àní, ó máa kígbe ogun;

Ó máa fi hàn pé òun lágbára ju àwọn ọ̀tá òun lọ.+

14 “Ó ti pẹ́ tí mo ti dákẹ́.

Mo dákẹ́ jẹ́ẹ́, mo sì kóra mi níjàánu.

Bí obìnrin tó fẹ́ bímọ,

Màá kérora, màá mí hẹlẹhẹlẹ, màá sì mí gúlegúle lẹ́ẹ̀kan náà.

15 Màá sọ àwọn òkè ńlá àti àwọn òkè kéékèèké di ahoro,

Màá sì mú kí gbogbo ewéko wọn gbẹ dà nù.

Màá sọ àwọn odò di erékùṣù,*

Màá sì mú kí àwọn adágún omi tí esùsú* kún inú wọn gbẹ táútáú.+

16 Màá mú àwọn afọ́jú gba ọ̀nà tí wọn ò mọ̀,+

Màá sì mú kí wọ́n gba ọ̀nà tó ṣàjèjì sí wọn.+

Màá sọ òkùnkùn tó wà níwájú wọn di ìmọ́lẹ̀,+

Màá sì sọ ilẹ̀ tó rí gbágungbàgun di ilẹ̀ tó tẹ́jú.+

Ohun tí màá ṣe fún wọn nìyí, mi ò sì ní fi wọ́n sílẹ̀.”

17 A máa dá wọn pa dà, ojú sì máa tì wọ́n gidigidi,

Àwọn tó gbẹ́kẹ̀ lé ère gbígbẹ́,

Àwọn tó ń sọ fún àwọn ère onírin* pé: “Ẹ̀yin ni ọlọ́run wa.”+

18 Ẹ fetí sílẹ̀, ẹ̀yin adití;

Ẹ wò, kí ẹ sì rí i, ẹ̀yin afọ́jú.+

19 Ta ló fọ́jú yàtọ̀ sí ìránṣẹ́ mi,

Tó dití bí ẹni tí mo rán níṣẹ́?

Ta ló fọ́jú bí ẹni tí a san lẹ́san,

Tó fọ́jú bí ìránṣẹ́ Jèhófà?+

20 O rí ọ̀pọ̀ nǹkan, àmọ́ o ò kíyè sí i.

O la etí rẹ sílẹ̀, àmọ́ o ò gbọ́.+

21 Nítorí òdodo rẹ̀,

Inú Jèhófà máa dùn láti mú kí òfin* níyì, kó sì ṣe é lógo.

22 Àmọ́ wọ́n ti kó àwọn èèyàn yìí lẹ́rù, wọ́n sì ti kó ohun ìní wọn lọ;+

Wọ́n ti sé gbogbo wọn mọ́ inú ihò, wọ́n sì ti fi wọ́n pa mọ́ sínú ẹ̀wọ̀n.+

Wọ́n ti kó ẹrù wọn láìsí ẹni tó máa gbà wọ́n sílẹ̀,+

Wọ́n sì ti kó ohun ìní wọn láìsí ẹni tó máa sọ pé: “Ẹ kó o pa dà!”

23 Ta ló máa gbọ́ èyí nínú yín?

Ta ló máa fiyè sílẹ̀, kó sì fetí sílẹ̀ torí àkókò tó ń bọ̀?

24 Ta ló ti mú kí wọ́n kó ohun ìní Jékọ́bù,

Tó sì mú kí wọ́n kó ẹrù Ísírẹ́lì?

Ṣebí Jèhófà ni, Ẹni tí a ṣẹ̀?

Wọ́n kọ̀ láti rìn ní àwọn ọ̀nà Rẹ̀,

Wọn ò sì ṣègbọràn sí òfin* Rẹ̀.+

25 Torí náà, Ó ń da ìhónú lé e lórí,

Ìrunú rẹ̀ àti ìbínú ogun.+

Ó jẹ gbogbo ohun tó yí i ká run, àmọ́ kò fiyè sí i.+

Ó jó o, àmọ́ kò fọkàn sí i.+

43 Ohun tí Jèhófà wá sọ nìyí,

Ẹlẹ́dàá rẹ, ìwọ Jékọ́bù, Ẹni tó dá ọ, ìwọ Ísírẹ́lì:+

“Má bẹ̀rù, torí mo ti tún ọ rà.+

Mo ti fi orúkọ rẹ pè ọ́.

Tèmi ni ọ́.

 2 Tí o bá gba inú omi kọjá, màá wà pẹ̀lú rẹ,+

Tí o bá sì gba inú odò kọjá, kò ní kún bò ọ́.+

Tí o bá rin inú iná kọjá, kò ní jó ọ,

Ọwọ́ iná ò sì ní rà ọ́.

 3 Torí èmi ni Jèhófà Ọlọ́run rẹ,

Ẹni Mímọ́ Ísírẹ́lì, Olùgbàlà rẹ.

Mo ti fi Íjíbítì ṣe ìràpadà fún ọ,

Mo sì ti fi Etiópíà àti Sébà dípò rẹ.

 4 Torí o ti wá ṣeyebíye ní ojú mi,+

A dá ọ lọ́lá, mo sì nífẹ̀ẹ́ rẹ.+

Torí náà, màá fi àwọn èèyàn rọ́pò rẹ,

Màá sì fi àwọn orílẹ̀-èdè dípò ẹ̀mí* rẹ.

  5 Má bẹ̀rù, torí mo wà pẹ̀lú rẹ.+

Màá mú ọmọ* rẹ wá láti ìlà oòrùn,

Màá sì kó ọ jọ láti ìwọ̀ oòrùn.+

 6 Màá sọ fún àríwá pé, ‘Dá wọn sílẹ̀!’+

Màá sì sọ fún gúúsù pé, ‘Má ṣe dá wọn dúró.

Mú àwọn ọmọkùnrin mi wá láti ọ̀nà jíjìn àti àwọn ọmọbìnrin mi láti àwọn ìkángun ayé,+

 7 Gbogbo ẹni tí wọ́n ń fi orúkọ mi pè,+

Tí mo sì dá fún ògo mi,

Tí mo ṣẹ̀dá, tí mo sì ṣe.’+

 8 Mú àwọn èèyàn tó fọ́jú jáde, bí wọ́n tiẹ̀ ní ojú,

Àwọn tó jẹ́ adití, bí wọ́n tiẹ̀ ní etí.+

 9 Kí gbogbo orílẹ̀-èdè pé jọ síbì kan,

Kí àwọn èèyàn sì kóra jọ.+

Èwo nínú wọn ló lè sọ èyí?

Àbí wọ́n lè mú ká gbọ́ àwọn ohun àkọ́kọ́?*+

Kí wọ́n mú àwọn ẹlẹ́rìí wọn wá, kí wọ́n lè fi hàn pé àwọn jàre,

Tàbí kí wọ́n gbọ́, kí wọ́n sì sọ pé, ‘Òótọ́ ni!’”+

10 “Ẹ̀yin ni ẹlẹ́rìí mi,”+ ni Jèhófà wí,

“Àní ìránṣẹ́ mi tí mo ti yàn,+

Kí ẹ lè mọ̀, kí ẹ sì ní ìgbàgbọ́ nínú mi,*

Kó sì yé yín pé Ẹnì kan náà ni mí.+

Ṣáájú mi, kò sí Ọlọ́run tí a dá,

Lẹ́yìn mi, kò sí ìkankan.+

11 Èmi, àní èmi ni Jèhófà,+ kò sí olùgbàlà kankan yàtọ̀ sí mi.”+

12 “Èmi ni Ẹni tó kéde, tó gbani là, tó sì mú kó di mímọ̀,

Nígbà tí kò sí ọlọ́run àjèjì kankan láàárín yín.+

Torí náà, ẹ̀yin ni ẹlẹ́rìí mi,” ni Jèhófà wí, “èmi sì ni Ọlọ́run.+

13 Bákan náà, Ẹnì kan náà ni mí+ nígbà gbogbo;

Kò sì sí ẹni tó lè já ohunkóhun gbà kúrò lọ́wọ́ mi.+

Tí mo bá ń ṣe nǹkan kan, ta ló lè dá mi dúró?”+

14 Ohun tí Jèhófà sọ nìyí, Olùtúnrà yín,+ Ẹni Mímọ́ Ísírẹ́lì:+

“Nítorí yín, màá ránṣẹ́ sí Bábílónì, màá sì gé gbogbo ọ̀pá ìdábùú ẹnubodè lulẹ̀,+

Àwọn ará Kálídíà sì máa ké jáde nínú ìdààmú, nínú àwọn ọkọ̀ òkun wọn.+

15 Èmi ni Jèhófà, Ẹni Mímọ́ yín,+ Ẹlẹ́dàá Ísírẹ́lì+ àti Ọba yín.”+

16 Ohun tí Jèhófà sọ nìyí,

Ẹni tó ń la ọ̀nà gba inú òkun,

Tó sì ń la ọ̀nà gba inú omi tó ń ru gùdù,+

17 Ẹni tó ń fa kẹ̀kẹ́ ogun àti ẹṣin jáde,+

Àwọn ọmọ ogun pẹ̀lú àwọn jagunjagun tó lákíkanjú:

“Wọ́n máa dùbúlẹ̀, wọn ò sì ní dìde.+

A máa fẹ́ wọn pa, a máa pa wọ́n bí òwú àtùpà tó ń jó.”

18 “Ẹ má ṣe rántí àwọn ohun àtijọ́,

Ẹ má sì máa ronú nípa ohun tó ti kọjá.

19 Ẹ wò ó! Mò ń ṣe ohun tuntun;+

Kódà, ní báyìí, ó ti ń rú yọ.

Ṣé ẹ ò mọ̀ ọ́n ni?

Màá la ọ̀nà kan gba inú aginjù,+

Màá sì mú kí odò gba inú aṣálẹ̀.+

20 Ẹran igbó máa bọlá fún mi,

Àwọn ajáko* àti ògòǹgò,

Torí mo pèsè omi ní aginjù,

Odò ní aṣálẹ̀,+

Fún àwọn èèyàn mi, àwọn àyànfẹ́ mi,+ kí wọ́n lè mu,

21 Àwọn èèyàn tí mo dá fún ara mi,

Kí wọ́n lè kéde ìyìn mi.+

22 Àmọ́ o ò ké pè mí, ìwọ Jékọ́bù,+

Torí ọ̀rọ̀ mi ti sú ọ, ìwọ Ísírẹ́lì.+

23 O ò mú àgùntàn wá fún mi láti fi rú àwọn odindi ẹbọ sísun rẹ,

O ò sì fi àwọn ẹbọ rẹ yìn mí lógo.

Mi ò fi dandan mú ọ pé kí o mú ẹ̀bùn wá fún mi,

Mi ò sì fi oje igi tùràrí tí mo ní kí o mú wá dá ọ lágara.+

24 O ò fi owó rẹ ra pòròpórò olóòórùn dídùn* fún mi,

O ò sì fi ọ̀rá àwọn ẹbọ rẹ tẹ́ mi lọ́rùn.+

Dípò ìyẹn, ṣe lo fi àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ di ẹrù wọ̀ mí lọ́rùn,

O sì fi àwọn àṣìṣe rẹ tán mi lókun.+

25 Èmi, àní èmi ni Ẹni tó ń nu àwọn àṣìṣe* rẹ+ kúrò nítorí tèmi,+

Mi ò sì ní rántí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ.+

26 Rán mi létí; jẹ́ ká gbé ẹjọ́ wa wá;

Ro ẹjọ́ rẹ, kí o lè fi hàn pé o jàre.

27 Baba ńlá rẹ àkọ́kọ́ ṣẹ̀,

Àwọn agbẹnusọ* rẹ sì ti ṣọ̀tẹ̀ sí mi.+

28 Torí náà, màá sọ àwọn ìjòyè ibi mímọ́ di aláìmọ́,

Màá mú kí wọ́n pa Jékọ́bù run,

Màá sì mú kí wọ́n sọ̀rọ̀ èébú sí Ísírẹ́lì.+

44 “Wá fetí sílẹ̀, ìwọ Jékọ́bù ìránṣẹ́ mi

Àti ìwọ Ísírẹ́lì, ẹni tí mo yàn.+

 2 Ohun tí Jèhófà sọ nìyí,

Aṣẹ̀dá rẹ àti Ẹni tó dá ọ,+

Ẹni tó ràn ọ́ lọ́wọ́ látinú oyún:*

‘Má bẹ̀rù, Jékọ́bù ìránṣẹ́ mi+

Àti ìwọ, Jéṣúrúnì,*+ ẹni tí mo yàn.

 3 Torí màá da omi sórí ẹni* tí òùngbẹ ń gbẹ,+

Màá sì mú kí odò ṣàn lórí ilẹ̀ gbígbẹ.

Màá da ẹ̀mí mi sórí ọmọ* rẹ +

Àti ìbùkún mi sórí àwọn àtọmọdọ́mọ rẹ.

 4 Wọ́n sì máa rú yọ bíi pé wọ́n yọ láàárín koríko tútù,+

Bí àwọn igi pọ́pílà ní etí omi tó ń ṣàn.

 5 Ẹnì kan máa sọ pé: “Ti Jèhófà ni mí.”+

Ẹlòmíì máa fi orúkọ Jékọ́bù pe ara rẹ̀,

Ẹlòmíì sì máa kọ ọ́ sí ọwọ́ rẹ̀ pé: “Ti Jèhófà.”

Á sì máa jẹ́ orúkọ Ísírẹ́lì.’

 6 Ohun tí Jèhófà sọ nìyí,

Ọba Ísírẹ́lì+ àti Olùtúnrà rẹ̀,+ Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun:

‘Èmi ni ẹni àkọ́kọ́ àti ẹni ìkẹyìn.+

Kò sí Ọlọ́run kankan àfi èmi.+

 7 Ta ló dà bí èmi?+

Kó pè, kó sọ ọ́, kó sì fi ẹ̀rí hàn mí!+

Látìgbà tí mo ti gbé àwọn èèyàn àtijọ́ kalẹ̀,

Jẹ́ kí wọ́n sọ àwọn ohun tó ń bọ̀

Àti ohun tí kò tíì ṣẹlẹ̀.

 8 Ẹ má ṣe jẹ́ kí jìnnìjìnnì bá yín,

Ẹ má sì jẹ́ kí ìbẹ̀rù sọ ọkàn yín domi.+

Ṣebí mo ti sọ fún ẹnì kọ̀ọ̀kan yín ṣáájú, tí mo sì kéde rẹ̀?

Ẹ̀yin ni ẹlẹ́rìí mi.+

Ṣé Ọlọ́run kankan wà yàtọ̀ sí mi ni?

Rárá, kò sí Àpáta míì;+ mi ò mọ ìkankan.’”

 9 Gbogbo àwọn tó ń ṣe ère gbígbẹ́ ò já mọ́ nǹkan kan,

Àwọn ohun tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ sí kò ní ṣàǹfààní rárá.+

Bí wọ́n tiẹ̀ jẹ́ ẹlẹ́rìí wọn, wọn* ò rí nǹkan kan, wọn ò sì mọ nǹkan kan,+

Torí náà, ojú máa ti àwọn tó ṣe wọ́n.+

10 Ta ló máa ṣe ọlọ́run tàbí kó ṣe ère onírin*

Tí kò lè ṣàǹfààní rárá?+

11 Wò ó! Ojú máa ti gbogbo àwọn alájọṣe rẹ̀!+

Èèyàn lásán ni àwọn oníṣẹ́ ọnà.

Kí gbogbo wọn kóra jọ, kí wọ́n sì dúró.

Jìnnìjìnnì máa bò wọ́n, ojú sì máa tì wọ́n pa pọ̀.

12 Alágbẹ̀dẹ ń fi irinṣẹ́ rẹ̀* lu irin lórí ẹyin iná.

Ó ń fi àwọn òòlù ṣe é,

Ó ń fi apá rẹ̀ tó lágbára ṣe é.+

Ebi wá ń pa á, okun sì tán nínú rẹ̀;

Kò mu omi, ó sì ti rẹ̀ ẹ́.

13 Agbẹ́gi na okùn ìdíwọ̀n, ó fi ẹfun pupa sàmì sí i.

Ó fi ìfági fá a, ó sì fi kọ́ńpáàsì sàmì sí i.

Ó ṣe é kó lè rí bí èèyàn,+

Ó mú kó rẹwà bí èèyàn,

Kó lè jókòó sínú ilé.*+

14 Ẹnì kan wà tó jẹ́ pé iṣẹ́ rẹ̀ ni kó máa gé igi kédárì lulẹ̀.

Ó mú oríṣi igi kan, ìyẹn igi ràgàjì,*

Ó sì jẹ́ kó di igi ńlá láàárín àwọn igi igbó.+

Ó gbin igi lọ̀rẹ́ẹ̀lì, òjò sì mú kó dàgbà.

15 Ó wá di ohun tí èèyàn lè fi dáná.

Ó mú lára rẹ̀, ó sì fi yáná;

Ó dá iná, ó sì yan búrẹ́dì.

Àmọ́ ó tún ṣe ọlọ́run kan, ó sì ń sìn ín.

Ó fi ṣe ère gbígbẹ́, ó sì ń forí balẹ̀ fún un.+

16 Ó fi iná sun ìdajì rẹ̀;

Ìdajì yẹn ló fi yan ẹran tó ń jẹ, ó sì yó.

Ó tún yáná, ó wá sọ pé:

“Áà! Ara mi ti móoru bí mo ṣe ń wo iná yìí.”

17 Àmọ́ ó fi èyí tó ṣẹ́ kù ṣe ọlọ́run, ó fi ṣe ère gbígbẹ́ fún ara rẹ̀.

Ó ń forí balẹ̀ fún un, ó sì ń sìn ín,

Ó ń gbàdúrà sí i, ó sì ń sọ pé:

“Gbà mí, torí ìwọ ni ọlọ́run mi.”+

18 Wọn ò mọ nǹkan kan, wọn ò lóye nǹkan kan,+

Torí a ti lẹ ojú wọn pa, wọn ò sì lè ríran,

Ọkàn wọn ò sì ní ìjìnlẹ̀ òye.

19 Kò sí ẹni tó rò ó nínú ọkàn rẹ̀,

Tó ní ìmọ̀ tàbí òye, pé:

“Mo ti dáná sun ìdajì rẹ̀,

Ẹyin iná rẹ̀ ni mo fi yan búrẹ́dì, tí mo sì fi yan ẹran tí màá jẹ.

Ṣé ó wá yẹ kí n fi èyí tó kù ṣe ohun ìríra?+

Ṣé ó yẹ kí n máa sin ìtì igi* tí mo gé lára igi?”

20 Ó ń jẹ eérú.

Ọkàn rẹ̀ tí wọ́n ti tàn jẹ ti kó o ṣìnà.

Kò lè gba ara* rẹ̀, kì í sì í sọ pé:

“Ṣé irọ́ kọ́ ló wà lọ́wọ́ ọ̀tún mi yìí?”

21 “Rántí àwọn nǹkan yìí, ìwọ Jékọ́bù àti ìwọ Ísírẹ́lì,

Torí pé ìránṣẹ́ mi ni ọ́.

Èmi ni mo dá ọ, ìránṣẹ́ mi sì ni ọ́.+

Ìwọ Ísírẹ́lì, mi ò ní gbàgbé rẹ.+

22 Màá nu àwọn àṣìṣe rẹ kúrò bíi pé mo fi ìkùukùu* nù ún,+

Màá sì nu àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ kúrò bíi pé mo fi àwọsánmà tó ṣú bolẹ̀ nù ún.

Pa dà sọ́dọ̀ mi, torí màá tún ọ rà.+

23 Ẹ kígbe ayọ̀, ẹ̀yin ọ̀run,

Torí Jèhófà ti ṣe nǹkan kan!

Ẹ kígbe ìṣẹ́gun, ẹ̀yin ibi tó jìn ní ilẹ̀!

Ẹ kígbe ayọ̀, ẹ̀yin òkè,+

Ẹ̀yin igbó àti gbogbo igi yín!

Torí Jèhófà ti tún Jékọ́bù rà,

Ó sì ń fi ẹwà rẹ̀ hàn lára Ísírẹ́lì.”+

24 Ohun tí Jèhófà sọ nìyí, Olùtúnrà rẹ,+

Ẹni tó dá ọ látìgbà tí o ti wà nínú oyún:

“Èmi ni Jèhófà, ẹni tó dá ohun gbogbo.

Èmi fúnra mi ni mo na ọ̀run,+

Mo sì tẹ́ ilẹ̀ ayé.+

Ta ló wà pẹ̀lú mi?

25 Màá mú kí iṣẹ́ àmì àwọn tó ń sọ̀rọ̀ asán* já sí pàbó,

Èmi sì ni Ẹni tó ń mú kí àwọn woṣẹ́woṣẹ́ máa ṣe bí òpònú;+

Ẹni tó ń da nǹkan rú mọ́ àwọn ọlọ́gbọ́n lójú,

Tó sì ń sọ ìmọ̀ wọn di ti òmùgọ̀;+

26 Ẹni tó ń mú kí ọ̀rọ̀ ìránṣẹ́ rẹ̀ ṣẹ,

Tó sì ń mú àsọtẹ́lẹ̀ àwọn òjíṣẹ́ rẹ̀ ṣẹ délẹ̀délẹ̀;+

Ẹni tó ń sọ nípa Jerúsálẹ́mù pé, ‘Wọ́n máa gbé inú rẹ̀’+

Àti nípa àwọn ìlú Júdà pé, ‘Wọ́n máa tún wọn kọ́,+

Màá sì mú kí àwọn ibi tó ti dahoro níbẹ̀ pa dà sí bó ṣe wà tẹ́lẹ̀’;+

27 Ẹni tó ń sọ fún ibú omi pé, ‘Gbẹ,

Màá sì mú kí gbogbo odò rẹ gbẹ táútáú’;+

28 Ẹni tó ń sọ nípa Kírúsì+ pé, ‘Òun ni olùṣọ́ àgùntàn mi,

Ó sì máa ṣe gbogbo ohun tí mo fẹ́ délẹ̀délẹ̀’;+

Ẹni tó ń sọ nípa Jerúsálẹ́mù pé, ‘Wọ́n máa tún un kọ́’

Àti nípa tẹ́ńpìlì pé, ‘Wọ́n máa fi ìpìlẹ̀ rẹ lélẹ̀.’”+

45 Ohun tí Jèhófà sọ fún ẹni tó yàn nìyí, fún Kírúsì,+

Ẹni tí mo di ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ mú,+

Láti tẹ àwọn orílẹ̀-èdè lórí ba níwájú rẹ̀,+

Láti gba ohun ìjà* àwọn ọba,

Láti ṣí àwọn ilẹ̀kùn aláwẹ́ méjì níwájú rẹ̀,

Kí wọ́n má sì ti àwọn ẹnubodè:

 2 “Màá lọ níwájú rẹ,+

Màá sì mú kí àwọn òkè di ilẹ̀ tó tẹ́jú.

Màá fọ́ àwọn ilẹ̀kùn bàbà sí wẹ́wẹ́,

Màá sì gé àwọn ọ̀pá irin lulẹ̀.+

 3 Màá fún ọ ní àwọn ìṣúra tó wà nínú òkùnkùn

Àti àwọn ìṣúra tó pa mọ́ láwọn ibi tí kò hàn síta,+

Kí o lè mọ̀ pé èmi ni Jèhófà,

Ọlọ́run Ísírẹ́lì, ẹni tó ń fi orúkọ rẹ pè ọ́.+

 4 Torí ìránṣẹ́ mi Jékọ́bù àti Ísírẹ́lì àyànfẹ́ mi,

Màá fi orúkọ rẹ pè ọ́.

Màá fún ọ ní orúkọ tó lọ́lá, bó ò tiẹ̀ mọ̀ mí.

 5 Èmi ni Jèhófà, kò sí ẹlòmíì.

Kò sí Ọlọ́run kankan yàtọ̀ sí mi.+

Màá fún ọ lókun,* bó ò tiẹ̀ mọ̀ mí,

 6 Kí àwọn èèyàn lè mọ̀,

Láti ibi tí oòrùn ti ń yọ, dé ibi tó ti ń wọ̀*

Pé kò sí ẹnì kankan yàtọ̀ sí mi.+

Èmi ni Jèhófà, kò sí ẹlòmíì.+

 7 Mo dá ìmọ́lẹ̀,+ mo sì ṣe òkùnkùn,+

Mo dá àlàáfíà,+ mo sì ṣe àjálù;+

Èmi Jèhófà ni mò ń ṣe gbogbo nǹkan yìí.

 8 Ẹ̀yin ọ̀run, ẹ rọ òjò sílẹ̀ látòkè;+

Kí ojú ọ̀run rọ òdodo sílẹ̀.

Kí ilẹ̀ lanu, kó sì so èso ìgbàlà,

Kó mú kí òdodo rú yọ lẹ́ẹ̀kan náà.+

Èmi Jèhófà ti dá a.”

 9 Ó mà ṣe fún ẹni tó ń bá Aṣẹ̀dá rẹ̀* fa nǹkan* o,

Torí ó dà bí àfọ́kù ìkòkò lásán

Láàárín àwọn àfọ́kù ìkòkò míì tó wà nílẹ̀!

Ṣé ó yẹ kí amọ̀ sọ fún Amọ̀kòkò* pé: “Kí lò ń mọ?”+

Àbí ó yẹ kí iṣẹ́ rẹ sọ pé: “Kò ní ọwọ́”?*

10 Ó mà ṣe o, fún ẹni tó ń sọ fún bàbá pé: “Kí lo bí?”

Àti fún obìnrin pé: “Kí lo fẹ́ bí?”*

11 Ohun tí Jèhófà sọ nìyí, Ẹni Mímọ́ Ísírẹ́lì,+ Ẹni tó dá a:

“Ṣé o máa bi mí nípa àwọn ohun tó ń bọ̀ ni,

Kí o sì pàṣẹ fún mi nípa àwọn ọmọ mi+ àti àwọn iṣẹ́ ọwọ́ mi?

12 Mo dá ayé,+ mo sì dá èèyàn sórí rẹ̀.+

Ọwọ́ ara mi ni mo fi na ọ̀run,+

Mo sì ń pàṣẹ fún gbogbo ọmọ ogun wọn.”+

13 “Mo ti gbé ẹnì kan dìde nínú òdodo,+

Màá sì mú kí gbogbo ọ̀nà rẹ̀ tọ́.

Òun ló máa kọ́ ìlú mi,+

Tó sì máa dá àwọn ìgbèkùn mi sílẹ̀ lọ́fẹ̀ẹ́ + tàbí láìgba àbẹ̀tẹ́lẹ̀,”+ ni Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun wí.

14 Ohun tí Jèhófà sọ nìyí:

“Èrè* Íjíbítì àti ọjà* Etiópíà àtàwọn Sábéà, àwọn tó ga,

Máa wá bá ọ, wọ́n á sì di tìrẹ.

Wọ́n á máa rìn lẹ́yìn rẹ, pẹ̀lú ṣẹkẹ́ṣẹkẹ̀ tí wọ́n fi dè wọ́n,

Wọ́n á wá bá ọ, wọ́n á sì tẹrí ba fún ọ.+

Wọ́n á gbàdúrà, wọ́n á sọ fún ọ pé, ‘Ó dájú pé Ọlọ́run wà pẹ̀lú rẹ,+

Kò sì sí ẹlòmíì; kò sí Ọlọ́run míì.’”

15 Lóòótọ́, Ọlọ́run tó ń fi ara rẹ̀ pa mọ́ ni ọ́,

Ìwọ Ọlọ́run Ísírẹ́lì, Olùgbàlà.+

16 Ojú máa ti gbogbo wọn, wọ́n sì máa tẹ́;

Ìtìjú ni gbogbo àwọn tó ń ṣe ère máa bá kúrò.+

17 Àmọ́ Jèhófà máa gba Ísírẹ́lì là, ìgbàlà náà sì máa jẹ́ títí láé.+

Ojú ò ní tì yín, ìtìjú ò sì ní bá yín títí ayé.+

18 Torí ohun tí Jèhófà sọ nìyí,

Ẹlẹ́dàá ọ̀run,+ Ọlọ́run tòótọ́,

Ẹni tó dá ayé, Aṣẹ̀dá rẹ̀ tó fìdí rẹ̀ múlẹ̀ gbọn-in,+

Ẹni tí kò kàn dá a lásán,* àmọ́ tó dá a ká lè máa gbé inú rẹ̀:+

“Èmi ni Jèhófà, kò sí ẹlòmíì.

19 Mi ò sọ̀rọ̀ ní ibi tó pa mọ́,+ ní ilẹ̀ tó ṣókùnkùn;

Mi ò sọ fún ọmọ* Jékọ́bù pé,

‘Ẹ kàn máa wá mi lásán.’*

Èmi ni Jèhófà, tó ń sọ ohun tó jẹ́ òdodo, tó sì ń kéde ohun tó tọ́.+

20 Ẹ kóra jọ, kí ẹ sì wá.

Ẹ jọ sún mọ́ tòsí, ẹ̀yin tí ẹ yè bọ́ látinú àwọn orílẹ̀-èdè.+

Wọn ò mọ nǹkan kan, àwọn tó ń gbé ère gbígbẹ́ kiri,

Tí wọ́n sì ń gbàdúrà sí ọlọ́run tí kò lè gbà wọ́n.+

21 Ẹ sọ tẹnu yín, ẹ ro ẹjọ́ yín.

Kí wọ́n fikùn lukùn ní ìṣọ̀kan.

Ta ló ti sọ èyí tipẹ́tipẹ́,

Tó sì kéde rẹ̀ láti ìgbà àtijọ́?

Ṣebí èmi, Jèhófà ni?

Kò sí Ọlọ́run míì, àfi èmi;

Ọlọ́run òdodo àti Olùgbàlà,+ kò sí ẹlòmíì yàtọ̀ sí mi.+

22 Ẹ yíjú sí mi, kí ẹ sì rí ìgbàlà,+ gbogbo ìkángun ayé.

Torí èmi ni Ọlọ́run, kò sí ẹlòmíì.+

23 Mo ti fi ara mi búra;

Ọ̀rọ̀ ti jáde lẹ́nu mi nínú òdodo,

Kò sì ní pa dà:+

Gbogbo eékún máa tẹ̀ ba fún mi,

Gbogbo ahọ́n máa búra láti dúró ṣinṣin,+

24 Wọ́n á sì sọ pé, ‘Ó dájú pé inú Jèhófà ni òdodo tòótọ́ àti okun wà.

Gbogbo àwọn tó ń bínú sí i máa fi ìtìjú wá síwájú rẹ̀.

25 Gbogbo ọmọ* Ísírẹ́lì máa fi hàn pé àwọn ṣe ohun tó tọ́ nínú Jèhófà,+

Òun ni wọ́n á sì máa fi yangàn.’”

46 Bélì bẹ̀rẹ̀ mọ́lẹ̀,+ Nébò tẹ̀ ba síwájú.

Wọ́n kó àwọn òrìṣà wọn sẹ́yìn àwọn ẹranko, sẹ́yìn àwọn ẹran akẹ́rù,+

Bí ẹrù tó ń ni àwọn ẹranko tó ti rẹ̀ lára.

 2 Wọ́n jọ tẹ̀ ba, wọ́n sì jọ bẹ̀rẹ̀ mọ́lẹ̀;

Wọn ò lè gba àwọn ẹrù* náà sílẹ̀,

Àwọn fúnra wọn* sì lọ sí ìgbèkùn.

 3 “Fetí sí mi, ìwọ ilé Jékọ́bù àti gbogbo ẹ̀yin tó ṣẹ́ kù ní ilé Ísírẹ́lì,+

Ẹ̀yin tí mò ń tì lẹ́yìn látìgbà tí a ti bí yín, tí mo sì gbé látinú oyún.+

 4 Títí o fi máa dàgbà, mi ò ní yí pa dà;+

Títí irun rẹ fi máa funfun, mi ò ní yéé gbé ọ.

Bí mo ti ń ṣe, màá gbé ọ, màá rù ọ́, màá sì gbà ọ́ sílẹ̀.+

 5 Ta lẹ lè fi mí wé, tí ẹ lè mú bá mi dọ́gba tàbí tí ẹ lè fi díwọ̀n mi,+

Tí a máa wá rí bákan náà?+

 6 Àwọn kan wà tó ń kó wúrà jáde yàlàyòlò látinú àpò wọn;

Wọ́n ń wọn fàdákà lórí òṣùwọ̀n.

Wọ́n gba oníṣẹ́ irin síṣẹ́, ó sì fi ṣe ọlọ́run.+

Wọ́n wá wólẹ̀, àní, wọ́n jọ́sìn rẹ̀.*+

 7 Wọ́n gbé e sí èjìká wọn,+

Wọ́n gbé e, wọ́n sì fi sí àyè rẹ̀, ṣe ló kàn dúró síbẹ̀.

Kì í kúrò ní àyè rẹ̀.+

Wọ́n ké sí i, àmọ́ kò dáhùn;

Kò lè gba ẹnikẹ́ni nínú wàhálà.+

 8 Ẹ rántí èyí, kí ẹ sì mọ́kàn le.

Ẹ fi sọ́kàn, ẹ̀yin ẹlẹ́ṣẹ̀.

 9 Ẹ rántí àwọn nǹkan àtijọ́* tó ti wà tipẹ́,

Pé èmi ni Ọlọ́run,* kò sí ẹlòmíì,

Èmi ni Ọlọ́run, kò sí ẹni tó dà bí èmi.+

10 Láti ìbẹ̀rẹ̀, mò ń sọ ohun tó máa ṣẹlẹ̀,

Tipẹ́tipẹ́ ni mo sì ti ń sọ àwọn ohun tí kò tíì ṣẹlẹ̀.+

Mo sọ pé, ‘Ìpinnu mi* máa dúró,+

Màá sì ṣe ohunkóhun tó bá wù mí.’+

11 Màá pe ẹyẹ aṣọdẹ wá láti ibi tí oòrùn ti ń yọ,*+

Ọkùnrin tó máa ṣe ohun tí mo pinnu*+ máa wá láti ilẹ̀ tó jìn.

Mo ti sọ̀rọ̀, màá sì mú kó ṣẹ.

Mo ti ní in lọ́kàn, màá sì ṣe é.+

12 Ẹ fetí sí mi, ẹ̀yin ọlọ́kàn líle,*

Ẹ̀yin tí ẹ jìnnà réré sí òdodo.

13 Mo ti mú òdodo mi sún mọ́ tòsí;

Kò jìnnà réré,

Ìgbàlà mi ò sì ní falẹ̀.+

Màá mú kí wọ́n rí ìgbàlà ní Síónì, ẹwà mi sì máa wà ní Ísírẹ́lì.”+

47 Sọ̀ kalẹ̀ wá jókòó sínú iyẹ̀pẹ̀,

Ìwọ wúńdíá ọmọbìnrin Bábílónì.+

Jókòó sílẹ̀ níbi tí kò sí ìtẹ́,+

Ìwọ ọmọbìnrin àwọn ará Kálídíà,

Torí àwọn èèyàn ò tún ní pè ọ́ ní ẹlẹgẹ́ àti àkẹ́jù mọ́.

 2 Mú ọlọ, kí o sì lọ ìyẹ̀fun.

Yọ ìbòjú rẹ.

Bọ́ aṣọ rẹ, ká aṣọ kúrò ní ẹsẹ̀ rẹ.

Sọdá àwọn odò.

 3 A máa tú ọ sí ìhòòhò.

Ìtìjú rẹ máa hàn síta.

Màá gbẹ̀san, + èèyàn kankan ò sì ní dá mi dúró.*

 4 “Ẹni tó ń tún wa rà,

Ni Ẹni Mímọ́ Ísírẹ́lì,+

Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun ni orúkọ rẹ̀.”

 5 Jókòó síbẹ̀, dákẹ́ jẹ́ẹ́, kí o sì lọ sínú òkùnkùn,

Ìwọ ọmọbìnrin àwọn ará Kálídíà;+

Wọn ò ní pè ọ́ ní Ìyálóde* Àwọn Ìjọba mọ́.+

 6 Inú bí mi sí àwọn èèyàn mi.+

Mo sọ ogún mi di aláìmọ́,+

Mo sì fi wọ́n lé ọ lọ́wọ́.+

Àmọ́ o ò ṣàánú wọn rárá.+

Kódà, o gbé àjàgà tó wúwo lé àgbàlagbà.+

 7 O sọ pé: “Títí láé ni màá jẹ́ Ìyálóde.”*+

O ò fi àwọn nǹkan yìí sọ́kàn;

O ò ro ibi tí ọ̀rọ̀ náà máa já sí.

 8 Wá gbọ́ èyí, ìwọ ẹni tó fẹ́ràn fàájì,+

Tó jókòó láìséwu, tó ń sọ lọ́kàn rẹ̀ pé:

“Èmi ni ẹni náà, kò sí ẹlòmíì.+

Mi ò ní di opó.

Mi ò ní ṣòfò ọmọ láé.”+

 9 Àmọ́ nǹkan méjèèjì yìí máa dé bá ọ lójijì, lọ́jọ́ kan ṣoṣo:+

Wàá ṣòfò ọmọ, wàá sì di opó.

Wọ́n máa dé bá ọ ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́,+

Torí* ọ̀pọ̀lọpọ̀ iṣẹ́ àjẹ́ rẹ àti gbogbo èèdì rẹ tó lágbára.+

10 O gbẹ́kẹ̀ lé ìwà burúkú rẹ.

O sọ pé: “Kò sẹ́ni tó ń rí mi.”

Ọgbọ́n àti ìmọ̀ rẹ ló kó ọ ṣìnà,

O sì ń sọ lọ́kàn rẹ pé: “Èmi ni ẹni náà, kò sí ẹlòmíì.”

11 Àmọ́ àjálù máa dé bá ọ,

Ìkankan nínú àwọn oògùn rẹ ò sì ní dá a dúró.*

O máa ko àgbákò; o ò ní lè yẹ̀ ẹ́.

Ìparun òjijì máa dé bá ọ, irú èyí tí kò ṣẹlẹ̀ sí ọ rí.+

12 Máa fi èèdì di àwọn èèyàn lọ, kí o sì máa ṣe ọ̀pọ̀lọpọ̀ iṣẹ́ àjẹ́ rẹ,+

Èyí tí o ti ń ṣe kára látìgbà ọ̀dọ́ rẹ.

Bóyá wàá lè jàǹfààní;

Bóyá wàá lè mú kí ẹ̀rù ba àwọn èèyàn.

13 Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn agbani-nímọ̀ràn rẹ ti tán ọ lókun.

Kí wọ́n dìde báyìí, kí wọ́n sì gbà ọ́ là,

Àwọn tó ń jọ́sìn ọ̀run,* tí wọ́n ń wo ìràwọ̀,+

Àwọn tó ń fúnni ní ìmọ̀ nígbà òṣùpá tuntun,

Nípa àwọn ohun tó máa ṣẹlẹ̀ sí ọ.

14 Wò ó! Wọ́n dà bí àgékù pòròpórò.

Iná máa jó wọn run.

Wọn ò lè gba ara* wọn lọ́wọ́ agbára ọwọ́ iná.

Àwọn èédú yìí kì í ṣe èyí tí a lè fi yáná,

Iná yìí kì í sì í ṣe èyí tí a lè jókòó síwájú rẹ̀.

15 Bẹ́ẹ̀ ni àwọn atujú rẹ máa rí sí ọ,

Àwọn tí ẹ jọ ṣiṣẹ́ kára látìgbà ọ̀dọ́ rẹ.

Wọ́n máa rìn gbéregbère, kálukú ní ọ̀nà tirẹ̀.*

Kò ní sí ẹni tó máa gbà ọ́ là.+

48 Gbọ́ èyí, ìwọ ilé Jékọ́bù,

Ẹ̀yin tí ẹ̀ ń fi orúkọ Ísírẹ́lì pe ara yín +

Àti ẹ̀yin tí ẹ jáde látinú omi* Júdà,

Ẹ̀yin tí ẹ̀ ń fi orúkọ Jèhófà búra,+

Tí ẹ sì ń ké pe Ọlọ́run Ísírẹ́lì,

Bó tiẹ̀ jẹ́ pé kì í ṣe ní òtítọ́ àti òdodo.+

 2 Torí wọ́n ń fi ìlú mímọ́+ pe ara wọn,

Wọ́n sì ń wá ìtìlẹyìn Ọlọ́run Ísírẹ́lì,+

Tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun.

 3 “Tipẹ́tipẹ́ ni mo ti sọ àwọn ohun àtijọ́* fún ọ.

Wọ́n ti ẹnu mi jáde,

Mo sì jẹ́ kó di mímọ̀.+

Mo gbé ìgbésẹ̀ lójijì, wọ́n sì ṣẹlẹ̀.+

 4 Torí mo mọ bí o ṣe lágídí tó,

Pé irin ni iṣan ọrùn rẹ àti pé bàbà ni iwájú orí rẹ,+

 5 Mo sọ fún ọ tipẹ́tipẹ́.

Kó tó ṣẹlẹ̀, mo mú kí o gbọ́ ọ,

Kí o má bàa sọ pé, ‘Òrìṣà mi ló ṣe èyí,

Ère gbígbẹ́ mi àti ère onírin* mi ló pa á láṣẹ.’

 6 Ẹ ti gbọ́, ẹ sì ti rí gbogbo èyí.

Ṣé ẹ ò ní kéde rẹ̀ ni?+

Láti ìsinsìnyí lọ, màá kéde àwọn ohun tuntun fún ọ,+

Àwọn àṣírí tí mo pa mọ́, tí o kò mọ̀.

 7 A ṣẹ̀ṣẹ̀ dá wọn ni, kì í ṣe látìgbà àtijọ́,

Àwọn ohun tí o ò gbọ́ rí kó tó di òní,

Kí o má bàa sọ pé, ‘Wò ó! Mo ti mọ̀ ọ́n tẹ́lẹ̀.’

 8 Rárá, o ò tíì gbọ́,+ o ò tíì mọ̀ ọ́n,

Etí rẹ ò sì là nígbà àtijọ́.

Nítorí mo mọ̀ pé ọ̀dàlẹ̀ paraku ni ọ́,+

A sì ti pè ọ́ ní ẹlẹ́ṣẹ̀ látìgbà tí wọ́n ti bí ọ.+

 9 Àmọ́ nítorí orúkọ mi, mi ò ní bínú mọ́;+

Nítorí ìyìn mi, màá kó ara mi níjàánu lórí ọ̀rọ̀ rẹ,

Mi ò sì ní pa ọ́ run.+

10 Wò ó! Mo ti yọ́ ọ mọ́, àmọ́ kì í ṣe bíi ti fàdákà.+

Mo ti dán ọ wò* nínú iná ìléru ti ìyà, tí a fi ń yọ́ nǹkan.+

11 Nítorí tèmi, àní nítorí tèmi, màá gbé ìgbésẹ̀,+

Ṣé màá wá jẹ́ kí wọ́n kẹ́gàn mi ni?+

Èmi kì í fi ògo mi fún ẹlòmíì.*

12 Fetí sí mi, ìwọ Jékọ́bù àti ìwọ Ísírẹ́lì, ẹni tí mo ti pè,

Ẹnì kan náà ni mí.+ Èmi ni ẹni àkọ́kọ́; èmi náà ni ẹni ìkẹyìn.+

13 Ọwọ́ mi ni mo fi fi ìpìlẹ̀ ayé sọlẹ̀,+

Ọwọ́ ọ̀tún mi ni mo sì fi na ọ̀run.+

Tí mo bá pè wọ́n, wọ́n jọ máa dìde.

14 Gbogbo yín, ẹ kóra jọ, kí ẹ sì fetí sílẹ̀.

Ta ni nínú wọn ló kéde àwọn nǹkan yìí?

Jèhófà nífẹ̀ẹ́ rẹ̀.+

Ó máa ṣe ohun tó dùn mọ́ ọn nínú sí Bábílónì,+

Apá rẹ̀ sì máa kọ lu àwọn ará Kálídíà.+

15 Èmi fúnra mi ti sọ̀rọ̀, mo sì ti pè é.+

Mo ti mú un wá, ọ̀nà rẹ̀ sì máa yọrí sí rere.+

16 Ẹ sún mọ́ mi, kí ẹ sì gbọ́ èyí.

Láti ìbẹ̀rẹ̀, mi ò sọ̀rọ̀ ní ìkọ̀kọ̀.+

Látìgbà tó ti ṣẹlẹ̀ ni mo ti wà níbẹ̀.”

Ní báyìí, Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ ti rán mi àti* ẹ̀mí rẹ̀.

17 Ohun tí Jèhófà sọ nìyí, Olùtúnrà rẹ, Ẹni Mímọ́ Ísírẹ́lì:+

“Èmi, Jèhófà, ni Ọlọ́run rẹ,

Ẹni tó ń kọ́ ọ kí o lè ṣe ara rẹ láǹfààní,*+

Ẹni tó ń jẹ́ kí o mọ ọ̀nà tó yẹ kí o máa rìn.+

18 Ká ní o fetí sí àwọn àṣẹ mi ni!+

Àlàáfíà rẹ ì bá dà bí odò,+

Òdodo rẹ ì bá sì dà bí ìgbì òkun.+

19 Àwọn ọmọ* rẹ ì bá pọ̀ bí erùpẹ̀ ilẹ̀,

Àwọn àtọmọdọ́mọ rẹ ì bá sì pọ̀ bí iyanrìn.+

A ò ní pa orúkọ wọn rẹ́ tàbí ká pa á run kúrò níwájú mi láé.”

20 Ẹ jáde kúrò ní Bábílónì!+

Ẹ sá kúrò lọ́dọ̀ àwọn ará Kálídíà!

Ẹ fi igbe ayọ̀ polongo rẹ̀! Ẹ kéde rẹ̀!+

Ẹ jẹ́ kó di mímọ̀ dé àwọn ìkángun ayé.+

Ẹ sọ pé: “Jèhófà ti tún Jékọ́bù ìránṣẹ́ rẹ̀ rà.+

21 Òùngbẹ ò gbẹ wọ́n nígbà tó mú wọn gba àwọn ibi tó ti pa run.+

Ó mú kí omi ṣàn jáde látinú àpáta fún wọn;

Ó la àpáta, ó sì mú kí omi rọ́ jáde.”+

22 Jèhófà sọ pé, “Kò sí àlàáfíà fún ẹni burúkú.”+

49 Ẹ fetí sí mi, ẹ̀yin erékùṣù,

Kí ẹ sì fiyè sílẹ̀, ẹ̀yin orílẹ̀-èdè tó jìnnà.+

Jèhófà ti pè mí kí wọ́n tó bí mi.*+

Ó ti dárúkọ mi látìgbà tí mo ti wà nínú ikùn ìyá mi.

 2 Ó ṣe ẹnu mi bí idà tó mú;

Ó fi mí pa mọ́ sínú òjìji ọwọ́ rẹ̀.+

Ó ṣe mí ní ọfà tó ń dán;

Ó fi mí pa mọ́ sínú apó rẹ̀.

 3 Ó sọ fún mi pé: “Ìránṣẹ́ mi ni ọ́, ìwọ Ísírẹ́lì,+

Ẹni tí màá tipasẹ̀ rẹ̀ fi ẹwà mi hàn.”+

 4 Àmọ́ mo sọ pé: “Lásán ni mo ṣe wàhálà.

Lásán ni mo lo okun mi tán lórí ohun tí kò sí rárá.

Àmọ́ ó dájú pé ìdájọ́ mi wà lọ́wọ́ Jèhófà,*

Èrè* mi sì wà lọ́dọ̀ Ọlọ́run mi.”+

 5 Ní báyìí, Jèhófà, Ẹni tó ṣe mí ní ìránṣẹ́ rẹ̀ látinú oyún,

Ti sọ pé kí n mú Jékọ́bù pa dà wá sọ́dọ̀ òun,

Kí a lè kó Ísírẹ́lì jọ sọ́dọ̀ rẹ̀.+

A máa ṣe mí lógo lójú Jèhófà,

Ọlọ́run mi á sì ti di okun mi.

 6 Ó sọ pé: “Ti pé o jẹ́ ìránṣẹ́ mi nìkan ò tó,

Láti gbé àwọn ẹ̀yà Jékọ́bù dìde,

Kí o sì mú àwọn tí a dá sí lára Ísírẹ́lì pa dà.

Mo tún ti fi ọ́ ṣe ìmọ́lẹ̀ àwọn orílẹ̀-èdè,+

Kí ìgbàlà mi lè dé gbogbo ayé.”+

7 Ohun tí Jèhófà, Olùtúnrà Ísírẹ́lì, Ẹni Mímọ́+ rẹ̀ sọ nìyí, fún ẹni tí wọ́n kórìíra,*+ ẹni tí orílẹ̀-èdè náà kórìíra, fún ìránṣẹ́ àwọn alákòóso:

“Àwọn ọba máa rí i, wọ́n sì máa dìde,

Àwọn ìjòyè máa tẹrí ba,

Nítorí Jèhófà, ẹni tó jẹ́ olóòótọ́,+

Ẹni Mímọ́ Ísírẹ́lì, ẹni tó yàn ọ́.”+

 8 Ohun tí Jèhófà sọ nìyí:

“Mo dá ọ lóhùn ní àkókò ojúure,*+

Mo sì ràn ọ́ lọ́wọ́ ní ọjọ́ ìgbàlà;+

Mò ń ṣọ́ ọ kí n lè fi ọ́ ṣe májẹ̀mú fún àwọn èèyàn náà,+

Láti tún ilẹ̀ náà ṣe,

Láti mú kí wọ́n gba àwọn ohun ìní wọn tó ti di ahoro,+

 9 Láti sọ fún àwọn ẹlẹ́wọ̀n pé, ‘Ẹ jáde wá!’+

Àti fún àwọn tó wà nínú òkùnkùn+ pé, ‘Ẹ fara hàn!’

Etí ọ̀nà ni wọ́n ti máa jẹun,

Ojú gbogbo ọ̀nà tó ti bà jẹ́* ni wọ́n ti máa jẹko.

10 Ebi ò ní pa wọ́n, òùngbẹ ò sì ní gbẹ wọ́n,+

Ooru tó ń jóni ò ní mú wọn, oòrùn ò sì ní pa wọ́n.+

Torí pé Ẹni tó ń ṣàánú wọn máa darí wọn,+

Ó sì máa mú wọn gba ibi àwọn ìsun omi.+

11 Màá sọ gbogbo òkè mi di ọ̀nà,

Àwọn ojú ọ̀nà mi sì máa ga sókè.+

12 Wò ó! Àwọn yìí ń bọ̀ láti ọ̀nà jíjìn,+

Sì wò ó! àwọn yìí ń bọ̀ láti àríwá àti ìwọ̀ oòrùn

Àti àwọn yìí láti ilẹ̀ Sínímù.”+

13 Ẹ kígbe ayọ̀, ẹ̀yin ọ̀run, sì máa yọ̀, ìwọ ayé.+

Kí inú àwọn òkè dùn, kí wọ́n sì kígbe ayọ̀.+

Torí Jèhófà ti tu àwọn èèyàn rẹ̀ nínú,+

Ó sì ń ṣàánú àwọn èèyàn rẹ̀ tí ìyà ń jẹ.+

14 Àmọ́ Síónì ń sọ ṣáá pé:

“Jèhófà ti pa mí tì,+ Jèhófà sì ti gbàgbé mi.”+

15 Ṣé obìnrin lè gbàgbé ọmọ rẹ̀ tó ṣì ń mu ọmú

Tàbí kó má ṣàánú ọmọ tó lóyún rẹ̀?

Tí àwọn obìnrin yìí bá tiẹ̀ gbàgbé, mi ò jẹ́ gbàgbé rẹ láé.+

16 Wò ó! Àtẹ́lẹwọ́ mi ni mo fín ọ sí.

Iwájú mi ni àwọn ògiri rẹ máa ń wà.

17 Àwọn ọmọ rẹ pa dà kíákíá.

Àwọn tó ya ọ́ lulẹ̀, tí wọ́n sì sọ ọ́ di ahoro máa kúrò lọ́dọ̀ rẹ.

18 Gbé ojú rẹ sókè, kí o sì wò yí ká.

Gbogbo wọn ń kóra jọ.+

Wọ́n ń bọ̀ lọ́dọ̀ rẹ.

“Bó ṣe dájú pé mo wà láàyè,” ni Jèhófà wí,

“O máa wọ gbogbo wọn bí ẹni wọ ohun ọ̀ṣọ́,

O sì máa dè wọ́n mọ́ra bíi ti ìyàwó.

19 Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn ilé rẹ ti pa run, ó ti di ahoro, ilẹ̀ rẹ sì ti di àwókù,+

Ó máa wá há jù fún àwọn tó ń gbé ibẹ̀,+

Àwọn tó gbé ọ mì káló+ sì máa jìnnà réré.+

20 Àwọn ọmọ tí wọ́n bí nígbà tí ọ̀fọ̀ ṣẹ̀ ọ́ máa sọ ní etí rẹ pé,

‘Ibí yìí ti há jù fún mi.

Wá àyè fún mi, kí n lè máa gbé ibí.’+

21 O sì máa sọ lọ́kàn rẹ pé,

‘Ta ni bàbá àwọn ọmọ mi yìí,

Ṣebí obìnrin tó ti ṣòfò ọmọ ni mí, tí mo sì yàgàn,

Tí mo lọ sí ìgbèkùn, tí wọ́n sì mú mi ní ẹlẹ́wọ̀n?

Ta ló tọ́ àwọn ọmọ yìí?+

Wò ó! Wọ́n fi èmi nìkan sílẹ̀,+

Ibo wá ni àwọn yìí ti wá?’”+

22 Ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí:

“Wò ó! Màá gbé ọwọ́ mi sókè sí àwọn orílẹ̀-èdè,

Màá sì gbé àmì* mi sókè sí àwọn èèyàn.+

Wọ́n máa fi ọwọ́ wọn gbé àwọn ọmọkùnrin rẹ wá,*

Wọ́n sì máa gbé àwọn ọmọbìnrin rẹ sí èjìká wọn.+

23 Àwọn ọba máa di olùtọ́jú rẹ,+

Àwọn ọmọ wọn obìnrin sì máa di alágbàtọ́ rẹ.

Wọ́n máa tẹrí ba fún ọ, wọ́n á sì dojú bolẹ̀,+

Wọ́n máa lá iyẹ̀pẹ̀ ẹsẹ̀ rẹ,+

Wàá sì mọ̀ pé èmi ni Jèhófà;

Ojú ò ní ti àwọn tó bá gbẹ́kẹ̀ lé mi.”+

24 Ṣé a lè gba àwọn tí alágbára ọkùnrin ti mú kúrò lọ́wọ́ rẹ̀,

Àbí ṣé a lè gba àwọn tí ìkà mú lẹ́rú sílẹ̀?

25 Àmọ́ ohun tí Jèhófà sọ nìyí:

“Kódà, a máa gba àwọn tí alágbára ọkùnrin mú lẹ́rú kúrò lọ́wọ́ rẹ̀,+

A sì máa gba àwọn tí ìkà mú sílẹ̀.+

Màá ta ko àwọn alátakò rẹ,+

Màá sì gba àwọn ọmọ rẹ là.

26 Màá mú kí àwọn tó ń fìyà jẹ ọ́ jẹ ẹran ara tiwọn,

Wọ́n sì máa mu ẹ̀jẹ̀ ara wọn yó bí ẹni mu wáìnì tó dùn.

Gbogbo èèyàn* sì máa mọ̀ pé èmi ni Jèhófà,+

Olùgbàlà rẹ+ àti Olùtúnrà rẹ,+

Alágbára Jékọ́bù.”+

50 Ohun tí Jèhófà sọ nìyí:

“Ìwé ẹ̀rí ìkọ̀sílẹ̀+ ìyá yín tí mo lé lọ dà?

Àbí èwo nínú àwọn tí mo jẹ ní gbèsè ni mo tà yín fún?

Ẹ wò ó! Torí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ yín+ ni mo ṣe tà yín,

Mo sì lé ìyá yín lọ torí àwọn àṣìṣe yín.+

 2 Kí ló wá dé tí kò sí ẹnì kankan níbí nígbà tí mo dé?

Kí ló dé tí ẹnì kankan ò dáhùn nígbà tí mo pè?+

Ṣé ọwọ́ mi kúrú jù láti rani pa dà ni,

Àbí mi ò lágbára láti gbani sílẹ̀ ni?+

Wò ó! Mo bá òkun wí, ó sì gbẹ táútáú;+

Mo sọ àwọn odò di aṣálẹ̀.+

Ẹja wọn jẹrà torí kò sí omi,

Wọ́n sì kú torí òùngbẹ.

 3 Mo fi ìṣúdùdù bo ọ̀run,+

Mo sì fi aṣọ ọ̀fọ̀* wọ̀ wọ́n.”

 4 Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ ti fún mi ní ahọ́n àwọn tí a kọ́,*+

Kí n lè mọ bó ṣe yẹ kí n fi ọ̀rọ̀ tó yẹ* dá ẹni tó ti rẹ̀ lóhùn.*+

Ó ń jí mi ní àràárọ̀;

Ó ń jí etí mi kí n lè fetí sílẹ̀ bí àwọn tí a kọ́.+

 5 Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ ti ṣí etí mi,

Mi ò sì ya ọlọ̀tẹ̀.+

Mi ò yíjú sí òdìkejì.+

 6 Mo tẹ́ ẹ̀yìn mi fún àwọn tó ń lù mí,

Mo sì gbé ẹ̀rẹ̀kẹ́ mi fún àwọn tó fa irun tu títí ó fi dán.*

Mi ò fi ojú mi pa mọ́ fún àwọn ohun tó ń dójú tini àti itọ́.+

 7 Àmọ́ Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ máa ràn mí lọ́wọ́.+

Ìdí nìyẹn tí ìtìjú ò fi ní bá mi.

Ìdí nìyẹn tí mo fi ṣe ojú mi bí akọ òkúta,+

Mo sì mọ̀ pé ojú ò ní tì mí.

 8 Ẹni tó ń pè mí ní olódodo wà nítòsí.

Ta ló lè fẹ̀sùn kàn mí?*+

Jẹ́ ká jọ dìde dúró.*

Ta ló fẹ́ bá mi ṣe ẹjọ́?

Kó sún mọ́ mi.

 9 Wò ó! Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ máa ràn mí lọ́wọ́.

Ta ló máa sọ pé mo jẹ̀bi?

Wò ó! Gbogbo wọn máa gbó bí aṣọ.

Òólá* ló máa jẹ wọ́n run.

10 Ta ló bẹ̀rù Jèhófà nínú yín,

Tó sì ń fetí sí ohùn ìránṣẹ́ rẹ̀?+

Ta ló ti rìn nínú òkùnkùn biribiri láìsí ìmọ́lẹ̀ kankan?

Kó gbẹ́kẹ̀ lé orúkọ Jèhófà, kó sì fara ti* Ọlọ́run rẹ̀.

11 “Ẹ wò ó! Gbogbo ẹ̀yin tí ẹ̀ ń dá iná,

Tí ẹ̀ ń mú kí iná ta pàrà,

Ẹ máa rìn nínú ìmọ́lẹ̀ iná yín,

Láàárín iná tí ẹ̀ ń mú kó ta pàrà.

Ohun tí ẹ máa gbà lọ́wọ́ mi nìyí:

Inú ìroragógó lẹ máa dùbúlẹ̀.

51 “Ẹ fetí sí mi, ẹ̀yin tí ẹ̀ ń lépa òdodo,

Ẹ̀yin tí ẹ̀ ń wá Jèhófà.

Ẹ yíjú sí àpáta tí a ti gbẹ́ yín jáde

Àti ibi tí wọ́n ti ń wa òkúta, tí a ti wà yín jáde.

 2 Ẹ yíjú sí Ábúráhámù bàbá yín

Àti Sérà+ tó bí yín.*

Torí ọ̀kan ṣoṣo ni nígbà tí mo pè é,+

Mo wá bù kún un, mo sì sọ ọ́ di púpọ̀.+

 3 Torí Jèhófà máa tu Síónì nínú.+

Ó máa tu gbogbo àwókù rẹ̀ nínú,+

Ó máa mú kí aginjù rẹ̀ rí bí Édẹ́nì,+

Ó sì máa mú kí aṣálẹ̀ rẹ̀ tó tẹ́jú rí bí ọgbà Jèhófà.+

Ìdùnnú àti ayọ̀ máa wà níbẹ̀,

Ìdúpẹ́ àti orin tó dùn.+

 4 Ẹ gbọ́ mi, ẹ̀yin èèyàn mi,

Kí o sì fetí sí mi, orílẹ̀-èdè mi.+

Torí òfin kan máa jáde látọ̀dọ̀ mi,+

Màá sì mú kí ìdájọ́ òdodo mi fìdí múlẹ̀ bí ìmọ́lẹ̀ fún àwọn èèyàn.+

 5 Òdodo mi sún mọ́lé.+

Ìgbàlà mi máa jáde lọ,+

Apá mi sì máa dá àwọn èèyàn lẹ́jọ́.+

Àwọn erékùṣù máa nírètí nínú mi,+

Wọ́n sì máa dúró de apá* mi.

 6 Ẹ gbé ojú yín sókè sí ọ̀run,

Kí ẹ sì wo ayé nísàlẹ̀.

Torí pé ọ̀run máa fẹ́ lọ bí èéfín;

Ayé máa gbó bí aṣọ,

Àwọn tó ń gbé ibẹ̀ sì máa kú bíi kòkòrò abìyẹ́ tó ń mùjẹ̀.

Àmọ́ ìgbàlà mi máa wà títí láé,+

Òdodo mi ò sì ní kùnà láéláé.*+

 7 Ẹ fetí sí mi, ẹ̀yin tó mọ òdodo,

Àwọn èèyàn tí òfin* mi wà lọ́kàn wọn.+

Ẹ má bẹ̀rù bí àwọn ẹni kíkú ṣe ń pẹ̀gàn yín,

Ẹ má sì jẹ́ kí èébú wọn kó jìnnìjìnnì bá yín.

 8 Torí pé òólá* máa jẹ wọ́n run bí aṣọ;

Òólá tó ń jẹ aṣọ* máa jẹ wọ́n run bí irun àgùntàn.+

Àmọ́ òdodo mi máa wà títí láé,

Ìgbàlà mi sì máa wà jálẹ̀ gbogbo ìran.”+

 9 Jí! Jí! Gbé agbára wọ̀,

Ìwọ apá Jèhófà! +

Jí, bíi ti àwọn ọjọ́ tó ti pẹ́, bíi ti àwọn ìran tó ti kọjá.

Ṣebí ìwọ lo fọ́ Ráhábù*+ sí wẹ́wẹ́,

Tí o gún ẹran ńlá inú òkun ní àgúnyọ?+

10 Ṣebí ìwọ lo mú kí òkun gbẹ, alagbalúgbú omi inú ibú?+

Ṣebí ìwọ lo sọ ibú òkun di ọ̀nà, tí àwọn tí a tún rà gbà sọdá?+

11 Àwọn tí Jèhófà rà pa dà máa pa dà.+

Wọ́n máa kígbe ayọ̀ wá sí Síónì,+

Ayọ̀ tí kò lópin sì máa dé wọn ládé.*+

Ìdùnnú àti ayọ̀ máa jẹ́ tiwọn,

Ẹ̀dùn ọkàn àti ìbànújẹ́ sì máa fò lọ.+

12 “Èmi fúnra mi ni Ẹni tó ń tù yín nínú.+

Ṣé ó wá yẹ kí ẹ máa bẹ̀rù ẹni kíkú tó máa kú+

Àti ọmọ aráyé tó máa rọ bíi koríko tútù?

13 Kí ló dé tí o gbàgbé Jèhófà Aṣẹ̀dá rẹ,+

Ẹni tó na ọ̀run,+ tó sì fi ìpìlẹ̀ ayé sọlẹ̀?

Ò ń bẹ̀rù ìbínú aninilára* ṣáá láti àárọ̀ ṣúlẹ̀,

Àfi bíi pé ó láṣẹ láti pa ọ́ run.

Ibo wá ni ìbínú aninilára wà?

14 Wọ́n máa tó dá ẹni tí wọ́n fi ẹ̀wọ̀n dè, tó sì tẹ̀ ba sílẹ̀;+

Kò ní kú, kò sì ní lọ sínú kòtò,

Oúnjẹ ò sì ní wọ́n ọn.

15 Àmọ́ èmi ni Jèhófà Ọlọ́run rẹ,

Ẹni tó ń ru òkun sókè, tó sì ń mú kí ìgbì rẹ̀ máa pariwo;+

Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun ni orúkọ rẹ̀.+

16 Màá fi ọ̀rọ̀ mi sí ẹnu rẹ,

Màá sì fi òjìji ọwọ́ mi bò ọ́,+

Kí n lè gbé ọ̀run kalẹ̀, kí n sì fi ìpìlẹ̀ ayé sọlẹ̀,+

Kí n sì sọ fún Síónì pé, ‘Èèyàn mi ni ọ́.’+

17 Jí! Jí! Dìde, ìwọ Jerúsálẹ́mù,+

Ìwọ tí o ti mu ife ìbínú Jèhófà láti ọwọ́ rẹ̀.

O ti mu látinú aago náà;

O ti mu ife tó ń múni ta gọ̀ọ́gọ̀ọ́ gbẹ.+

18 Ìkankan nínú gbogbo ọmọ tó bí kò sí níbẹ̀ láti darí rẹ̀,

Kò sì sí ìkankan nínú gbogbo ọmọ tó tọ́ dàgbà tó di ọwọ́ rẹ̀ mú.

19 Ohun méjì yìí ti dé bá ọ.

Ta ló máa bá ọ kẹ́dùn?

Ìparun àti ìsọdahoro, ebi àti idà!+

Ta ló máa tù ọ́ nínú?+

20 Àwọn ọmọ rẹ ti dákú.+

Wọ́n dùbúlẹ̀ sí gbogbo oríta* ojú ọ̀nà

Bí àgùntàn igbó tó wà nínú àwọ̀n.

Ìbínú Jèhófà kún inú wọn, ìbáwí Ọlọ́run rẹ.”

21 Torí náà, jọ̀ọ́, fetí sí èyí,

Ìwọ obìnrin tí ìyà ń jẹ, tó sì ti yó, àmọ́ tí kì í ṣe wáìnì ló mu.

22 Ohun tí Olúwa rẹ, Jèhófà sọ nìyí, Ọlọ́run rẹ, tó ń gbèjà àwọn èèyàn rẹ̀:

“Wò ó! Màá gba ife tó ń múni ta gọ̀ọ́gọ̀ọ́ kúrò lọ́wọ́ rẹ,+

Aago náà, ife ìbínú mi;

O ò ní mu ún mọ́ láé.+

23 Màá fi sí ọwọ́ àwọn tó ń dá ọ lóró,+

Àwọn tó sọ fún ọ* pé, ‘Tẹ̀ ba ká lè rìn lórí rẹ!’

O wá sọ ẹ̀yìn rẹ di ilẹ̀,

Bí ojú ọ̀nà tí wọ́n máa rìn kọjá.”

52 Jí! Jí! Gbé agbára wọ̀,+ ìwọ Síónì!+

Wọ aṣọ rẹ tó rẹwà,+ ìwọ Jerúsálẹ́mù, ìlú mímọ́!

Torí ẹni tí kò dádọ̀dọ́* àti aláìmọ́ kò ní wọ inú rẹ mọ́.+

 2 Gbọn eruku kúrò, gbéra kí o sì jókòó, ìwọ Jerúsálẹ́mù.

Tú ìdè ọrùn rẹ, ìwọ ọmọbìnrin Síónì tí wọ́n mú lẹ́rú.+

 3 Torí ohun tí Jèhófà sọ nìyí:

“Ọ̀fẹ́ ni wọ́n tà yín,+

A sì máa tún yín rà láìsan owó.”+

 4 Torí ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí:

“Àwọn èèyàn mi kọ́kọ́ lọ sí Íjíbítì, wọ́n sì gbé níbẹ̀ bí àjèjì;+

Ásíríà wá fìyà jẹ wọ́n láìnídìí.”

 5 “Kí wá ni kí n ṣe níbí?” ni Jèhófà wí.

“Ọ̀fẹ́ ni wọ́n kó àwọn èèyàn mi lọ.

Àwọn tó ń jọba lé wọn lórí ń kígbe pé àwọn ti ṣẹ́gun,”+ ni Jèhófà wí,

“Nígbà gbogbo, láti àárọ̀ ṣúlẹ̀, wọn ò bọ̀wọ̀ fún orúkọ mi.+

 6 Ìyẹn máa mú kí àwọn èèyàn mi mọ orúkọ mi;+

Ìyẹn máa mú kí wọ́n mọ̀ ní ọjọ́ yẹn pé èmi ni Ẹni tó ń sọ̀rọ̀.

Wò ó, èmi ni!”

 7 Wo bí ẹsẹ̀ ẹni tó ń mú ìhìn rere wá ṣe rẹwà tó lórí àwọn òkè,+

Ẹni tó ń kéde àlàáfíà,+

Ẹni tó ń mú ìhìn rere wá nípa ohun tó sàn,

Ẹni tó ń kéde ìgbàlà,

Ẹni tó ń sọ fún Síónì pé: “Ọlọ́run rẹ ti di Ọba!”+

 8 Fetí sílẹ̀! Àwọn olùṣọ́ rẹ gbé ohùn wọn sókè.

Wọ́n kígbe ayọ̀ níṣọ̀kan,

Torí wọ́n máa rí i kedere* tí Jèhófà bá pa dà kó Síónì jọ.

 9 Ẹ tújú ká, ẹ kígbe ayọ̀ níṣọ̀kan, ẹ̀yin àwókù Jerúsálẹ́mù,+

Torí Jèhófà ti tu àwọn èèyàn rẹ̀ nínú;+ ó ti tún Jerúsálẹ́mù rà.+

10 Jèhófà ti jẹ́ kí wọ́n rí apá rẹ̀ mímọ́ lójú gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè;+

Gbogbo ìkángun ayé sì máa rí bí Ọlọ́run wa ṣe ń gbani là.*+

11 Ẹ yíjú pa dà, ẹ yíjú pa dà, ẹ jáde kúrò níbẹ̀,+ ẹ má fọwọ́ kan ohun àìmọ́ kankan!+

Ẹ jáde kúrò ní àárín rẹ̀,+ ẹ wà ní mímọ́,

Ẹ̀yin tí ẹ̀ ń gbé àwọn ohun èlò Jèhófà.+

12 Ẹ ò ní fi ìbẹ̀rù lọ,

Ẹ ò sì ní sá lọ,

Torí Jèhófà máa ṣáájú yín,+

Ọlọ́run Ísírẹ́lì á sì máa ṣọ́ yín láti ẹ̀yìn.+

13 Wò ó! Ìránṣẹ́ mi+ máa fi ìjìnlẹ̀ òye hùwà.

A máa gbé e ga,

A máa gbé e lékè, a sì máa gbé e ga gidigidi.+

14 Bó ṣe jẹ́ pé ọ̀pọ̀ ló ń wò ó tìyanutìyanu,

Tí wọ́n ba ìrísí rẹ̀ jẹ́ ju ti èèyàn èyíkéyìí míì,

Tí wọ́n sì ba ìrísí rẹ̀ tó buyì kún un jẹ́ ju ti ọmọ aráyé,

15 Bẹ́ẹ̀ ni òun náà máa dẹ́rù ba ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè.+

Àwọn ọba máa pa ẹnu wọn mọ́* níwájú rẹ̀,+

Torí wọ́n máa rí ohun tí wọn ò tíì sọ fún wọn,

Wọ́n sì máa ronú nípa ohun tí wọn ò tíì gbọ́.+

53 Ta ló ti nígbàgbọ́ nínú ohun tó gbọ́ lọ́dọ̀ wa?*+

Ní ti apá Jèhófà,+ ta la ti fi hàn?+

 2 Ó máa jáde wá bí ẹ̀ka igi+ níwájú rẹ̀,* bíi gbòǹgbò látinú ilẹ̀ tó gbẹ táútáú.

Ìrísí rẹ̀ kò buyì kún un, kò sì rẹwà rárá;+

Tí a bá sì rí i, ìrísí rẹ̀ kò fà wá sún mọ́ ọn.*

 3 Àwọn èèyàn kórìíra rẹ̀, wọ́n sì yẹra fún un,+

Ọkùnrin tó mọ bí ìrora ṣe ń rí,* tó sì mọ àìsàn dunjú.

Ó dà bí ẹni pé ojú rẹ̀ pa mọ́ fún wa.*

Wọ́n kórìíra rẹ̀, a sì kà á sí ẹni tí kò já mọ́ nǹkan kan.+

 4 Lóòótọ́, òun fúnra rẹ̀ gbé àwọn àìsàn wa,+

Ó sì ru àwọn ìrora wa.+

Àmọ́ a kà á sí ẹni tí ìyọnu bá, ẹni tí Ọlọ́run kọ lù, tó sì ń jìyà.

 5 Wọ́n gún un+ torí àṣìṣe wa;+

Wọ́n tẹ̀ ẹ́ rẹ́ torí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa.+

Ó jìyà ká lè ní àlàáfíà,+

A sì rí ìwòsàn nítorí àwọn ọgbẹ́ rẹ̀.+

 6 Gbogbo wa ti rìn gbéregbère bí àgùntàn,+

Kálukú ti yíjú sí ọ̀nà tirẹ̀,

Jèhófà sì ti mú kó ru ẹ̀ṣẹ̀ gbogbo wa.+

 7 Wọ́n ni ín lára,+ ó sì jẹ́ kí wọ́n fìyà jẹ òun,+

Àmọ́ kò la ẹnu rẹ̀.

Wọ́n mú un wá bí àgùntàn sí ibi tí wọ́n ti fẹ́ pa á,+

Bí abo àgùntàn tó dákẹ́ níwájú àwọn tó ń rẹ́ irun rẹ̀,

Kò sì la ẹnu rẹ̀.+

 8 Wọ́n mú un lọ torí àìṣẹ̀tọ́* àti ìdájọ́;

Ta ló sì máa da ara rẹ̀ láàmú nípa kúlẹ̀kúlẹ̀ ìran rẹ̀?*

Torí wọ́n mú un kúrò lórí ilẹ̀ alààyè;+

Ó jẹ ìyà* torí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn èèyàn mi.+

 9 Wọ́n sin ín* pẹ̀lú àwọn ẹni burúkú+

Àti àwọn ọlọ́rọ̀,* nígbà tó kú,+

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò ṣe ohunkóhun tí kò dáa,*

Kò sì sí ẹ̀tàn kankan lẹ́nu rẹ̀.+

10 Àmọ́ ó wu Jèhófà* láti tẹ̀ ẹ́ rẹ́, ó sì jẹ́ kó ṣàìsàn.

Tí o bá máa fi ẹ̀mí* rẹ̀ rú ẹbọ ẹ̀bi,+

Ó máa rí ọmọ* rẹ̀, ó máa mú kí àwọn ọjọ́ rẹ̀ gùn,+

Ohun tí inú Jèhófà dùn sí* sì máa yọrí sí rere nípasẹ̀ rẹ̀.+

11 Torí ìrora* rẹ̀, ó máa rí i, ó sì máa tẹ́ ẹ lọ́rùn.

Nípasẹ̀ ìmọ̀ rẹ̀, ìránṣẹ́ mi+ tó jẹ́ olódodo

Máa mú kí a ka ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn sí olódodo,+

Ó sì máa ru àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wọn.+

12 Torí ìyẹn, màá fún un ní ìpín láàárín ọ̀pọ̀lọpọ̀,

Ó sì máa pín ẹrù ogun pẹ̀lú àwọn alágbára,

Torí ó tú ẹ̀mí* rẹ̀ jáde, àní títí dé ikú,+

Wọ́n sì kà á mọ́ àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀;+

Ó ru ẹ̀ṣẹ̀ ọ̀pọ̀ èèyàn,+

Ó sì bá àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ bẹ̀bẹ̀.+

54 “Kígbe ayọ̀, ìwọ àgàn tí kò bímọ!+

Tújú ká, kí o sì kígbe ayọ̀,+ ìwọ tí o kò ní ìrora ìbímọ rí,+

Torí àwọn ọmọ* ẹni tó ti di ahoro pọ̀

Ju àwọn ọmọ obìnrin tó ní ọkọ,”*+ ni Jèhófà wí.

 2 “Mú kí ibi àgọ́ rẹ fẹ̀ sí i.+

Na àwọn aṣọ àgọ́ rẹ tó tóbi.

Má fawọ́ sẹ́yìn, mú kí àwọn okùn àgọ́ rẹ gùn sí i,

Kí o sì jẹ́ kí àwọn èèkàn àgọ́ rẹ lágbára.+

 3 Torí pé o máa tàn sí apá ọ̀tún àti sí apá òsì.

Àwọn ọmọ rẹ máa gba àwọn orílẹ̀-èdè,

Wọ́n sì máa gbé àwọn ìlú tó ti di ahoro.+

 4 Má bẹ̀rù,+ torí ojú ò ní tì ọ́;+

Má sì jẹ́ kí ìtìjú bá ọ, torí o ò ní rí ìjákulẹ̀.

Torí o máa gbàgbé ìtìjú ìgbà ọ̀dọ́ rẹ,

O ò sì ní rántí bí ojú ṣe tì ọ́ nígbà opó rẹ mọ́.”

 5 “Torí pé Aṣẹ̀dá rẹ Atóbilọ́lá+ dà bí ọkọ* rẹ,+

Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun ni orúkọ rẹ̀,

Ẹni Mímọ́ Ísírẹ́lì sì ni Olùtúnrà rẹ.+

Ọlọ́run gbogbo ayé la ó máa pè é.+

 6 Torí Jèhófà pè ọ́ bí ìyàwó tí wọ́n pa tì, tí ẹ̀dùn ọkàn sì bá,*+

Bí ìyàwó tí wọ́n fẹ́ nígbà ọ̀dọ́, tí wọ́n wá kọ̀ sílẹ̀,” ni Ọlọ́run rẹ wí.

 7 “Torí mo pa ọ́ tì fún ìgbà díẹ̀,

Àmọ́ màá ṣàánú rẹ gidigidi, màá sì kó ọ jọ pa dà.+

 8 Mo fi ojú mi pa mọ́ fún ọ fún àkókò díẹ̀ torí inú bí mi gidigidi,+

Àmọ́ màá ṣàánú rẹ nítorí ìfẹ́ tí kì í yẹ̀, tó wà títí láé,”+ ni Jèhófà, Olùtúnrà rẹ+ wí.

 9 “Bí àwọn ọjọ́ Nóà ló ṣe rí sí mi.+

Bí mo ṣe búra pé omi Nóà ò ní bo ayé mọ́,+

Bẹ́ẹ̀ náà ni mo búra pé mi ò ní bínú sí ọ mọ́, mi ò sì ní bá ọ wí mọ́.+

10 Àwọn òkè ńlá lè ṣí kúrò,

Àwọn òkè kéékèèké sì lè mì tìtì,

Àmọ́ ìfẹ́ mi tí kì í yẹ̀ ò ní kúrò lọ́dọ̀ rẹ,+

Májẹ̀mú àlàáfíà mi ò sì ní mì,”+ ni Jèhófà, Ẹni tó ń ṣàánú rẹ wí.+

11 “Ìwọ obìnrin tí ìyà ń jẹ,+ tí ìjì ń gbé síwá-sẹ́yìn, tí a kò tù nínú,+

Màá fi àpòrọ́ líle mọ àwọn òkúta rẹ,

Màá sì fi sàfáyà ṣe ìpìlẹ̀ rẹ.+

12 Òkúta rúbì ni màá fi ṣe odi orí òrùlé rẹ,

Àwọn òkúta tó ń tàn yinrin* ni màá fi ṣe àwọn ẹnubodè rẹ,

Màá sì fi àwọn òkúta iyebíye ṣe gbogbo ààlà rẹ.

13 Jèhófà máa kọ́ gbogbo àwọn ọmọ* rẹ,+

Àlàáfíà àwọn ọmọ* rẹ sì máa pọ̀ gan-an.+

14 O máa fìdí múlẹ̀ gbọn-in nínú òdodo.+

Ìnilára máa jìnnà réré sí ọ,+

O ò ní bẹ̀rù ohunkóhun, ohunkóhun ò sì ní já ọ láyà,

Torí pé kò ní sún mọ́ ọ.+

15 Tí ẹnikẹ́ni bá gbéjà kò ọ́,

Èmi kọ́ ni mo pa á láṣẹ.

Ẹnikẹ́ni tó bá gbéjà kò ọ́ máa ṣubú nítorí rẹ.”+

16 “Wò ó! Èmi fúnra mi ni mo dá oníṣẹ́ ọnà,

Ẹni tó ń fẹ́ atẹ́gùn sí iná èédú,

Tí iṣẹ́ rẹ̀ sì mú ohun ìjà jáde.

Èmi náà ni mo dá apanirun tó ń pani run.+

17 Ohun ìjà èyíkéyìí tí wọ́n bá ṣe sí ọ kò ní ṣàṣeyọrí,+

Ahọ́n èyíkéyìí tó bá sì dìde sí ọ láti dá ọ lẹ́jọ́ ni wàá dá lẹ́bi.

Ogún* àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà nìyí,

Ọ̀dọ̀ mi sì ni òdodo wọn ti wá,” ni Jèhófà wí.+

55 Ẹ wá, gbogbo ẹ̀yin tí òùngbẹ ń gbẹ,+ ẹ wá síbi omi!+

Ẹ̀yin tẹ́ ò ní owó, ẹ wá, ẹ rà, kí ẹ sì jẹ!

Àní, ẹ wá, ẹ ra wáìnì àti wàrà+ lọ́fẹ̀ẹ́, láìsan owó.+

 2 Kí ló dé tí ẹ fi ń sanwó fún ohun tí kì í ṣe oúnjẹ,

Kí ló sì dé tí ẹ fi ń lo ohun tí ẹ ṣiṣẹ́ fún* sórí ohun tí kì í tẹ́ni lọ́rùn?

Ẹ tẹ́tí sí mi dáadáa, kí ẹ sì jẹ ohun tó dáa,+

Ohun tó dọ́ṣọ̀* sì máa mú inú yín dùn* gidigidi.+

 3 Ẹ dẹ etí yín sílẹ̀, kí ẹ sì wá sọ́dọ̀ mi.+

Ẹ fetí sílẹ̀, ẹ* ó sì máa wà láàyè nìṣó,

Ó sì dájú pé màá bá yín dá májẹ̀mú tó máa wà títí láé+

Bí mo ṣe fi ìfẹ́ tí kì í yẹ̀, tó jẹ́ òótọ́,* hàn sí Dáfídì.+

 4 Wò ó! Mo fi ṣe ẹlẹ́rìí+ fún àwọn orílẹ̀-èdè,

Aṣáájú+ àti aláṣẹ+ àwọn orílẹ̀-èdè.

 5 Wò ó! O máa pe orílẹ̀-èdè tí o kò mọ̀,

Àwọn èèyàn orílẹ̀-èdè tí kò mọ̀ ọ́ sì máa sáré wá sọ́dọ̀ rẹ,

Torí Jèhófà Ọlọ́run rẹ,+ Ẹni Mímọ́ Ísírẹ́lì,

Torí pé ó máa ṣe ọ́ lógo.+

 6 Ẹ wá Jèhófà nígbà tí ẹ lè rí i.+

Ẹ pè é nígbà tó wà nítòsí.+

 7 Kí èèyàn burúkú fi ọ̀nà rẹ̀ sílẹ̀,+

Kí ẹni ibi sì yí èrò rẹ̀ pa dà;

Kó pa dà sọ́dọ̀ Jèhófà, ẹni tó máa ṣàánú rẹ̀,+

Sọ́dọ̀ Ọlọ́run wa, torí ó máa dárí jini fàlàlà.*+

 8 “Torí èrò mi yàtọ̀ sí èrò yín,+

Ọ̀nà yín sì yàtọ̀ sí ọ̀nà mi,” ni Jèhófà wí.

 9 “Torí bí ọ̀run ṣe ga ju ayé lọ,

Bẹ́ẹ̀ ni ọ̀nà mi ga ju ọ̀nà yín,

Èrò mi sì ga ju èrò yín.+

10 Torí bí òjò àti yìnyín ṣe ń rọ̀ láti ọ̀run gẹ́lẹ́,

Tí kì í sì í pa dà síbẹ̀, àfi tó bá mú kí ilẹ̀ rin, tó jẹ́ kó méso jáde, kí nǹkan sì hù,

Tó jẹ́ kí ẹni tó fúnrúgbìn ká irúgbìn, tí ẹni tó ń jẹun sì rí oúnjẹ,

11 Bẹ́ẹ̀ ni ọ̀rọ̀ mi tó ti ẹnu mi jáde máa rí.*+

Kò ní pa dà sọ́dọ̀ mi láìṣẹ,+

Àmọ́ ó dájú pé ó máa ṣe ohunkóhun tí inú mi bá dùn sí,*+

Ó sì dájú pé ohun tí mo rán an pé kó ṣe máa yọrí sí rere.

12 Ẹ máa fi ayọ̀ jáde lọ,+

A sì máa mú yín pa dà ní àlàáfíà.+

Àwọn òkè ńlá àtàwọn òkè kéékèèké máa fi igbe ayọ̀ túra ká níwájú yín,+

Gbogbo àwọn igi inú igbó sì máa pàtẹ́wọ́.+

13 Dípò àwọn igi ẹlẹ́gùn-ún, igi júnípà máa hù,+

Dípò èsìsì tó ń jóni lára, igi mátílì máa hù.

Ó sì máa mú kí Jèhófà lókìkí,*+

Àmì tó máa wà títí láé, tí kò ní pa run.”

56 Ohun tí Jèhófà sọ nìyí:

“Ẹ máa ṣe ìdájọ́ òdodo,+ kí ẹ sì máa ṣe òdodo,

Torí ìgbàlà mi máa tó dé,

A sì máa ṣí òdodo mi payá.+

 2 Aláyọ̀ ni ẹni tó ń ṣe èyí

Àti ọmọ èèyàn tó rọ̀ mọ́ ọn,

Tó ń pa Sábáàtì mọ́, tí kò sì kẹ́gàn rẹ̀,+

Tí kò sì fi ọwọ́ rẹ̀ ṣe ohunkóhun tó burú.

 3 Àjèjì tó bá fara mọ́ Jèhófà+ ò gbọ́dọ̀ sọ pé,

‘Ó dájú pé Jèhófà máa yà mí sọ́tọ̀ kúrò lára àwọn èèyàn rẹ̀.’

Ìwẹ̀fà ò sì gbọ́dọ̀ sọ pé, ‘Wò ó! Igi gbígbẹ ni mí.’”

4 Torí ohun tí Jèhófà sọ fún àwọn ìwẹ̀fà nìyí, àwọn tó ń pa àwọn sábáàtì mi mọ́, tí wọ́n yan ohun tí inú mi dùn sí, tí wọ́n sì rọ̀ mọ́ májẹ̀mú mi:

 5 “Màá fún wọn ní ohun ìrántí àti orúkọ ní ilé mi àti lára àwọn ògiri mi,

Ohun tó dára ju àwọn ọmọkùnrin àtàwọn ọmọbìnrin.

Màá fún wọn ní orúkọ tó máa wà títí láé,

Èyí tí kò ní pa run.

 6 Ní ti àwọn àjèjì tó fara mọ́ Jèhófà láti máa ṣe ìránṣẹ́ fún un,

Láti nífẹ̀ẹ́ orúkọ Jèhófà,+

Kí wọ́n sì di ìránṣẹ́ rẹ̀,

Gbogbo àwọn tó ń pa Sábáàtì mọ́, tí wọn ò sì kẹ́gàn rẹ̀,

Tí wọ́n ń rọ̀ mọ́ májẹ̀mú mi,

 7 Màá tún mú wọn wá sí òkè mímọ́ mi,+

Màá sì mú kí wọ́n máa yọ̀ nínú ilé àdúrà mi.

Màá tẹ́wọ́ gba odindi ẹbọ sísun wọn àtàwọn ẹbọ wọn lórí pẹpẹ mi.

Torí a ó máa pe ilé mi ní ilé àdúrà fún gbogbo èèyàn.”+

8 Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ, ẹni tó ń kó àwọn tó fọ́n ká lára Ísírẹ́lì jọ,+ kéde pé:

“Màá kó àwọn míì jọ sọ́dọ̀ rẹ̀ yàtọ̀ sí àwọn tí a ti kó jọ tẹ́lẹ̀.”+

 9 Gbogbo ẹ̀yin ẹranko inú pápá, ẹ wá jẹun,

Gbogbo ẹ̀yin ẹran inú igbó.+

10 Afọ́jú ni àwọn olùṣọ́ rẹ̀,+ ìkankan nínú wọn ò kíyè sí i.+

Ajá tí kò lè fọhùn ni gbogbo wọn, wọn ò lè gbó.+

Wọ́n ń mí hẹlẹ, wọ́n sì dùbúlẹ̀; wọ́n fẹ́ràn oorun.

11 Ajá tó ń jẹun wọ̀mùwọ̀mù* ni wọ́n;

Wọn kì í yó.

Olùṣọ́ àgùntàn tí kò lóye ni wọ́n.+

Gbogbo wọn ti bá ọ̀nà tiwọn lọ;

Àní ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn ń wá èrè tí kò tọ́ fún ara rẹ̀, ó ń sọ pé:

12 “Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí n mu wáìnì díẹ̀,

Ẹ sì jẹ́ ká mu ọtí yó.+

Bí òní ṣe rí ni ọ̀la máa rí, ó tiẹ̀ máa dáa gan-an jù ú lọ!”

57 Olódodo ṣègbé,

Àmọ́ ẹnì kankan ò fi sọ́kàn.

Àwọn olóòótọ́ èèyàn ti lọ,*+

Ẹnì kankan ò sì fòye mọ̀ pé olódodo ti lọ

Torí* àjálù náà.

 2 Ó wọnú àlàáfíà.

Wọ́n sinmi lórí ibùsùn wọn,* gbogbo àwọn tó ń rìn lọ́nà títọ́.

 3 “Àmọ́ ní tiyín, ẹ sún mọ́ tòsí,

Ẹ̀yin ọmọ àjẹ́,

Ẹ̀yin ọmọ alágbèrè àti aṣẹ́wó:

 4 Ta lẹ fi ń ṣe yẹ̀yẹ́?

Ta lẹ la ẹnu gbàù sí, tí ẹ sì yọ ahọ́n yín sí?

Ṣebí ọmọ ẹ̀ṣẹ̀ ni yín,

Ẹ̀yin ọmọ ẹ̀tàn,+

 5 Tí ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ti kó sí lórí láàárín àwọn igi ńlá,+

Lábẹ́ gbogbo igi tó gbẹ̀rẹ̀gẹ̀jigẹ̀,+

Ẹ̀yin tí ẹ̀ ń pa àwọn ọmọ ní àwọn àfonífojì,+

Lábẹ́ àwọn pàlàpálá àpáta?

 6 Ìpín rẹ wà níbi àwọn òkúta tó jọ̀lọ̀ ní àfonífojì.+

Àní, àwọn ni ìpín rẹ.

Kódà, àwọn lò ń da ọrẹ ohun mímu sí, tí o sì ń mú ẹ̀bùn wá fún.+

Ṣé àwọn nǹkan yìí máa tẹ́ mi lọ́rùn?*

 7 Orí òkè tó ga, tó ta yọ lo gbé ibùsùn rẹ sí,+

O sì gòkè lọ síbẹ̀ láti rúbọ.+

 8 Ẹ̀yìn ilẹ̀kùn àti férémù ilẹ̀kùn lo gbé ìrántí rẹ kalẹ̀ sí.

O fi mí sílẹ̀, o sì ṣí ara rẹ sílẹ̀;

O lọ, o sì mú kí ibùsùn rẹ fẹ̀ dáadáa.

O sì bá wọn dá májẹ̀mú.

O máa ń fẹ́ bá wọn pín ibùsùn wọn,+

O sì ń wo nǹkan ọkùnrin.*

 9 O sọ̀ kalẹ̀ lọ sọ́dọ̀ Mélékì* pẹ̀lú òróró

Àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ lọ́fínńdà.

O rán àwọn aṣojú rẹ lọ sọ́nà jíjìn,

Tí o fi sọ̀ kalẹ̀ lọ sínú Isà Òkú.*

10 O ti ṣiṣẹ́ kára láti rìn ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọ̀nà rẹ.

Àmọ́ o ò sọ pé, ‘Kò sírètí!’

A wá sọ agbára rẹ dọ̀tun.

Ìdí nìyẹn tí o kò fi sọ̀rètí nù.*

11 Ta ló ń já ọ láyà, tí ẹ̀rù rẹ̀ sì ń bà ọ́,

Tí o fi bẹ̀rẹ̀ sí í parọ́?+

O ò rántí mi.+

O ò fi nǹkan kan sọ́kàn.+

Ṣebí mo ti dákẹ́, tí mo sì fà sẹ́yìn?*+

O ò wá bẹ̀rù mi rárá.

12 Màá fi ‘òdodo’+ rẹ àti àwọn iṣẹ́ rẹ+ hàn,

Wọn ò sì ní ṣe ọ́ láǹfààní.+

13 Tí o bá kígbe fún ìrànlọ́wọ́,

Àwọn òrìṣà tí o kó jọ ò ní gbà ọ́ sílẹ̀.+

Atẹ́gùn máa gbé gbogbo wọn lọ,

Èémí lásán máa fẹ́ wọn lọ,

Àmọ́ ẹni tó bá fi mí ṣe ibi ààbò máa jogún ilẹ̀ náà,

Ó sì máa gba òkè mímọ́ mi.+

14 Wọ́n máa sọ pé, ‘Ẹ ṣe ọ̀nà, ẹ ṣe é! Ẹ tún ọ̀nà ṣe!+

Ẹ mú gbogbo ohun ìdíwọ́ kúrò ní ọ̀nà àwọn èèyàn mi.’”

15 Torí ohun tí Ẹni Gíga àti Ẹni Tó Ta Yọ sọ nìyí,

Tó wà láàyè* títí láé,+ tí orúkọ rẹ̀ sì jẹ́ mímọ́:+

“Ibi gíga àti ibi mímọ́ ni mò ń gbé,+

Àmọ́ mo tún ń gbé pẹ̀lú àwọn tí a tẹ̀ rẹ́, tí wọ́n sì rẹ̀wẹ̀sì ní ẹ̀mí,

Láti mú kí ẹ̀mí ẹni tó rẹlẹ̀ sọ jí,

Kí n sì mú kí ọkàn àwọn tí a tẹ̀ rẹ́ sọ jí.+

16 Torí mi ò ní ta kò wọ́n títí láé,

Mi ò sì ní máa bínú títí lọ;+

Torí àárẹ̀ máa bá ẹ̀mí èèyàn nítorí mi,+

Títí kan àwọn ohun tó ń mí, tí mo dá.

17 Inú bí mi torí ẹ̀ṣẹ̀ tó dá, bó ṣe ń wá èrè tí kò tọ́,+

Torí náà, mo kọ lù ú, mo fi ojú mi pa mọ́, inú sì bí mi.

Àmọ́ kò yéé rìn bí ọ̀dàlẹ̀,+ ó ń ṣe ìfẹ́ ọkàn rẹ̀.

18 Mo ti rí àwọn ọ̀nà rẹ̀,

Àmọ́ màá wò ó sàn,+ màá sì darí rẹ̀,+

Màá mú kí òun àti àwọn èèyàn rẹ̀+ tó ń ṣọ̀fọ̀ pa dà rí ìtùnú.”*+

19 “Màá dá èso ètè.

Màá fún ẹni tó wà lọ́nà jíjìn àti ẹni tó wà nítòsí ní àlàáfíà tí kò lópin,”+ ni Jèhófà wí,

“Màá sì wò ó sàn.”

20 “Àmọ́ àwọn ẹni burúkú dà bí òkun tó ń ru, tí kò lè rọ̀ wọ̀ọ̀,

Omi rẹ̀ sì ń ta koríko inú òkun àti ẹrẹ̀ sókè.

21 Kò sí àlàáfíà fún ẹni burúkú,”+ ni Ọlọ́run mi wí.

58 “Fi gbogbo ẹnu kígbe; má ṣe dákẹ́!

Gbé ohùn rẹ sókè bíi fèrè.

Kéde ọ̀tẹ̀ àwọn èèyàn mi fún wọn,+

Kí o sọ àwọn ẹ̀ṣẹ̀ ilé Jékọ́bù fún wọn.

 2 Wọ́n ń wá mi lójoojúmọ́,

Inú wọn sì ń dùn láti mọ àwọn ọ̀nà mi,

Bíi pé orílẹ̀-èdè olódodo ni wọ́n,

Tí kò sì pa ìdájọ́ òdodo Ọlọ́run wọn tì.+

Wọ́n béèrè ìdájọ́ òdodo lọ́wọ́ mi,

Inú wọn ń dùn láti sún mọ́ Ọlọ́run:+

 3 ‘Kí ló dé tí o ò rí i nígbà tí à ń gbààwẹ̀?+

Kí ló sì dé tí o ò kíyè sí i nígbà tí à ń pọ́n ara* wa lójú?’+

Torí ní ọjọ́ tí ẹ̀ ń gbààwẹ̀, ire* ara yín lẹ̀ ń wá,

Ẹ sì ń fìyà jẹ àwọn alágbàṣe yín.+

 4 Aáwọ̀ àti ìjà ló máa ń gbẹ̀yìn ààwẹ̀ yín,

Ẹ sì ń gbáni ní ẹ̀ṣẹ́ ìkà.

Ẹ ò lè gbààwẹ̀ bí ẹ ṣe ń ṣe lónìí, kí a sì gbọ́ ohùn yín ní ọ̀run.

 5 Ṣé ó yẹ kí ààwẹ̀ tí mo fọwọ́ sí rí báyìí,

Bí ọjọ́ tí èèyàn máa pọ́n ara* rẹ̀ lójú,

Tó máa dorí kodò bí koríko etídò,

Kó ṣe ibùsùn rẹ̀ sórí aṣọ ọ̀fọ̀* àti eérú?

Ṣé ohun tí ẹ̀ ń pè ní ààwẹ̀ àti ọjọ́ tínú Jèhófà dùn sí nìyí?

 6 Rárá, ààwẹ̀ tí mo fọwọ́ sí nìyí:

Kí ẹ tú ṣẹkẹ́ṣẹkẹ̀ ìkà,

Kí ẹ tú ìdè ọ̀pá àjàgà,+

Kí ẹ tú ẹni tí ìyà ń jẹ sílẹ̀,+

Kí ẹ sì kán gbogbo ọ̀pá àjàgà sí méjì;

 7 Ẹ fún ẹni tí ebi ń pa lára oúnjẹ yín,+

Kí ẹ mú aláìní àti ẹni tí kò rílé gbé wá sínú ilé yín,

Kí ẹ fi aṣọ bo ẹni tó wà ní ìhòòhò tí ẹ bá rí i,+

Kí ẹ má sì kẹ̀yìn sí àwọn èèyàn yín.

 8 Ìmọ́lẹ̀ rẹ máa wá tàn bí ọ̀yẹ̀,+

Ìwòsàn rẹ sì máa yára dé.

Òdodo rẹ á máa lọ níwájú rẹ,

Ògo Jèhófà á sì máa ṣọ́ ọ láti ẹ̀yìn.+

 9 O máa pè, Jèhófà sì máa dáhùn;

O máa kígbe fún ìrànlọ́wọ́, ó sì máa sọ pé, ‘Èmi nìyí!’

Tí o bá mú ọ̀pá àjàgà kúrò láàárín rẹ,

Tí o kò na ìka rẹ, tí o kò sì sọ̀rọ̀ ìbàjẹ́ mọ́,+

10 Tí o bá fún ẹni tí ebi ń pa ní ohun tí ìwọ fúnra rẹ* fẹ́,+

Tí o sì tẹ́ àwọn* tí ìyà ń jẹ lọ́rùn,

Ìmọ́lẹ̀ rẹ máa tàn nínú òkùnkùn pàápàá,

Ìṣúdùdù rẹ sì máa dà bí ọ̀sán gangan.+

11 Jèhófà á máa darí rẹ nígbà gbogbo,

Ó sì máa tẹ́ ọ* lọ́rùn, kódà ní ilẹ̀ gbígbẹ;+

Ó máa mú kí egungun rẹ lágbára,

O sì máa dà bí ọgbà tí wọ́n ń bomi rin dáadáa,+

Bí ìsun omi, tí omi rẹ̀ kì í tán.

12 Wọ́n máa tún àwọn àwókù àtijọ́ kọ́ nítorí rẹ,+

O sì máa dá ìpìlẹ̀ àwọn ìran tó ti kọjá pa dà sí bó ṣe wà tẹ́lẹ̀.+

Wọ́n máa pè ọ́ ní ẹni tó ń tún àwọn ògiri tó ti fọ́ ṣe,*+

Ẹni tó ń ṣe àtúnṣe àwọn ọ̀nà tí wọ́n á máa gbé.

13 Tí o kò bá wá* ire ara rẹ* ní ọjọ́ mímọ́ mi, nítorí Sábáàtì,+

Tí o sì pe Sábáàtì ní ohun tó ń múnú ẹni dùn gidigidi, ọjọ́ mímọ́ Jèhófà, ọjọ́ tó yẹ ká ṣe lógo,+

Tí o sì ṣe é lógo dípò kí o máa wá ire ara rẹ, kí o sì máa sọ ọ̀rọ̀ tí kò nítumọ̀,

14 Nígbà náà, inú rẹ máa dùn gidigidi torí Jèhófà,

Màá sì mú kí o gun àwọn ibi tó ga ní ayé.+

Màá mú kí o jẹ nínú* ogún Jékọ́bù baba ńlá rẹ,+

Torí Jèhófà ti fi ẹnu rẹ̀ sọ ọ́.”

59 Wò ó! Ọwọ́ Jèhófà kò kúrú jù láti gbani là,+

Bẹ́ẹ̀ ni etí rẹ̀ kò di* tí kò fi lè gbọ́.+

 2 Rárá, àwọn àṣìṣe yín ti pín ẹ̀yin àti Ọlọ́run yín níyà.+

Àwọn ẹ̀ṣẹ̀ yín ti mú kó fi ojú rẹ̀ pa mọ́ fún yín,

Ó sì kọ̀ láti gbọ́ yín.+

 3 Torí ẹ̀jẹ̀ ti sọ àtẹ́lẹwọ́ yín di eléèérí,+

Ẹ̀ṣẹ̀ sì ti sọ ìka yín di eléèérí.

Ètè yín ń parọ́,+ ahọ́n yín sì ń sọ àìṣòdodo kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́.

 4 Kò sí ẹni tó ń wá òdodo,+

Kò sí ẹni tó ń fi òótọ́ inú lọ sí ilé ẹjọ́.

Ohun tí kò sí rárá* ni wọ́n gbẹ́kẹ̀ lé,+ wọ́n sì ń sọ ohun tí kò ní láárí.

Wọ́n lóyún wàhálà, wọ́n sì bí ohun tó ń pani lára.+

 5 Wọ́n pa ẹyin ejò olóró,

Wọ́n sì hun òwú aláǹtakùn.+

Ẹnikẹ́ni tó bá jẹ ẹyin wọn máa kú,

Ẹyin tí wọ́n sì tẹ̀ fọ́ mú ejò paramọ́lẹ̀ jáde.

 6 Òwú aláǹtakùn wọn ò ní dà bí aṣọ,

Wọn ò sì ní fi ohun tí wọ́n ṣe bo ara wọn.+

Iṣẹ́ wọn léwu,

Ìwà ipá ló sì kún ọwọ́ wọn.+

 7 Ẹsẹ̀ wọn ń sáré láti hùwà burúkú,

Wọ́n sì ń yára láti ta ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ sílẹ̀.+

Ohun burúkú ni wọ́n ń rò;

Ìparun àti ìyà wà ní àwọn ọ̀nà wọn.+

 8 Wọn ò mọ ọ̀nà àlàáfíà,

Kò sí ìdájọ́ òdodo ní àwọn ipa ọ̀nà wọn.+

Wọ́n mú kí àwọn ọ̀nà wọn wọ́;

Ìkankan nínú àwọn tó ń rìn níbẹ̀ kò ní mọ àlàáfíà.+

 9 Ìdí nìyẹn tí ìdájọ́ òdodo fi jìnnà sí wa,

Tí òdodo kò sì lé wa bá.

À ń retí ìmọ́lẹ̀ ṣáá, àmọ́ wò ó! òkùnkùn ló ṣú;

À ń retí ìmọ́lẹ̀ tó tàn yòò, àmọ́ a ò yéé rìn nínú ìṣúdùdù.+

10 À ń táràrà níbi ògiri bí afọ́jú;

À ń táràrà bí àwọn tí kò ní ojú.+

A kọsẹ̀ ní ọ̀sán gangan bíi pé a wà nínú òkùnkùn alẹ́;

Ṣe la dà bí òkú láàárín àwọn alágbára.

11 Gbogbo wa ń kùn ṣáá bíi bíárì,

A sì ń ṣọ̀fọ̀, à ń ké kúùkúù bí àdàbà.

À ń retí ìdájọ́ òdodo, àmọ́ kò sí;

À ń retí ìgbàlà, àmọ́ ó jìnnà gan-an sí wa.

12 Torí ọ̀tẹ̀ wa pọ̀ níwájú rẹ;+

Àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa ń ta kò wá níkọ̀ọ̀kan.+

Torí àwọn ọ̀tẹ̀ wa wà pẹ̀lú wa;

A mọ àwọn àṣìṣe wa dáadáa.+

13 A ti ṣẹ̀, a sì ti sẹ́ Jèhófà;

A ti kẹ̀yìn sí Ọlọ́run wa,

A ti sọ̀rọ̀ nípa ìnilára àti ọ̀tẹ̀;+

A ti lóyún irọ́, a sì ti sọ̀rọ̀ èké kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́ látinú ọkàn.+

14 Wọ́n ti rọ́ ìdájọ́ òdodo sẹ́yìn,+

Òdodo sì dúró sí ọ̀nà jíjìn;+

Nítorí pé òtítọ́* ti kọsẹ̀ ní ojúde ìlú,

Ohun tó tọ́ kò sì rí ọ̀nà wọlé.

15 Òtítọ́* ti pòórá,+

Ẹnikẹ́ni tó bá sì yí pa dà kúrò nínú ohun tó burú ni wọ́n ń kó lẹ́rù.

Jèhófà rí i, inú rẹ̀ ò sì dùn*

Torí kò sí ìdájọ́ òdodo.+

16 Ó rí i pé kò sí èèyàn kankan,

Ó sì yà á lẹ́nu pé ẹnì kankan ò bá wọn bẹ̀bẹ̀,

Torí náà, apá rẹ̀ mú ìgbàlà wá,*

Òdodo rẹ̀ sì tì í lẹ́yìn.

17 Ó wá gbé òdodo wọ̀ bí ẹ̀wù irin,

Ó sì dé akoto ìgbàlà* sí orí rẹ̀.+

Ó wọ ẹ̀wù ẹ̀san bí aṣọ,+

Ó sì fi ìtara bo ara rẹ̀ bí aṣọ àwọ̀lékè.*

18 Ó máa san wọ́n lẹ́san ohun tí wọ́n ṣe:+

Ó máa bínú sí àwọn elénìní rẹ̀, ó máa fi ìyà ẹ̀ṣẹ̀ jẹ àwọn ọ̀tá rẹ̀.+

Ó sì máa san ohun tó yẹ àwọn erékùṣù fún wọn.

19 Wọ́n máa bẹ̀rù orúkọ Jèhófà láti ìwọ̀ oòrùn

Àti ògo rẹ̀ láti ìlà oòrùn,

Torí ó máa wọlé wá bí odò tó ń yára ṣàn,

Tí ẹ̀mí Jèhófà ń gbé lọ.

20 “Olùtúnrà+ máa wá sí Síónì,+

Sọ́dọ̀ àwọn ti Jékọ́bù, àwọn tó yí pa dà kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀,”+ ni Jèhófà wí.

21 “Ní tèmi, májẹ̀mú tí mo bá wọn dá nìyí,”+ ni Jèhófà wí. “Ẹ̀mí mi tó wà lára rẹ àti àwọn ọ̀rọ̀ mi tí mo fi sí ẹnu rẹ kò ní kúrò ní ẹnu rẹ, ní ẹnu àwọn ọmọ* rẹ tàbí ní ẹnu àwọn ọmọ ọmọ rẹ,”* ni Jèhófà wí, “láti ìsinsìnyí lọ àti títí láé.”

60 “Dìde, ìwọ obìnrin,+ tan ìmọ́lẹ̀, torí ìmọ́lẹ̀ rẹ ti dé.

Ògo Jèhófà ń tàn sára rẹ.+

 2 Torí, wò ó! òkùnkùn máa bo ayé,

Ìṣúdùdù tó kàmàmà sì máa bo àwọn orílẹ̀-èdè;

Àmọ́ Jèhófà máa tàn sára rẹ,

Wọ́n sì máa rí ògo rẹ̀ lára rẹ.

 3 Àwọn orílẹ̀-èdè máa lọ sínú ìmọ́lẹ̀ rẹ,+

Àwọn ọba+ sì máa lọ sínú ẹwà rẹ tó ń tàn.*+

 4 Gbé ojú rẹ sókè, kí o sì wò yí ká!

Gbogbo wọn ti kóra jọ; wọ́n ń bọ̀ lọ́dọ̀ rẹ.

Àwọn ọmọkùnrin rẹ ń bọ̀ láti ọ̀nà jíjìn,+

Ẹ̀gbẹ́ ni wọ́n sì gbé àwọn ọmọbìnrin rẹ sí.+

 5 Ní àkókò yẹn, o máa rí i, o sì máa tàn yinrin,+

Ọkàn rẹ máa lù kìkì, ó sì máa kún rẹ́rẹ́,

Torí pé a máa darí ọrọ̀ òkun sọ́dọ̀ rẹ;

Àwọn ohun àmúṣọrọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè máa wá sọ́dọ̀ rẹ.+

 6 Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ràkúnmí máa bo ilẹ̀ rẹ,*

Àwọn akọ ọmọ ràkúnmí Mídíánì àti Eéfà.+

Gbogbo àwọn tó wá láti Ṣébà, wọ́n máa wá;

Wọ́n máa gbé wúrà àti oje igi tùràrí.

Wọ́n máa kéde ìyìn Jèhófà.+

 7 A máa kó gbogbo agbo ẹran Kídárì+ jọ sọ́dọ̀ rẹ.

Àwọn àgbò Nébáótì+ máa sìn ọ́.

Wọ́n máa wá sórí pẹpẹ mi pẹ̀lú ìtẹ́wọ́gbà,+

Màá sì ṣe ilé ológo mi* lọ́ṣọ̀ọ́.+

 8 Àwọn wo nìyí tí wọ́n ń fò kọjá bí ìkùukùu,

Bí àwọn àdàbà tó ń fò lọ sí ilé* wọn?

 9 Torí àwọn erékùṣù máa gbẹ́kẹ̀ lé mi,+

Àwọn ọkọ̀ òkun Táṣíṣì ló ṣíwájú,*

Láti kó àwọn ọmọ rẹ wá láti ọ̀nà jíjìn,+

Pẹ̀lú fàdákà wọn àti wúrà wọn,

Síbi orúkọ Jèhófà Ọlọ́run rẹ àti sọ́dọ̀ Ẹni Mímọ́ Ísírẹ́lì,

Torí ó máa ṣe ọ́ lógo.*+

10 Àwọn àjèjì máa mọ àwọn ògiri rẹ,

Àwọn ọba wọn sì máa ṣe ìránṣẹ́ fún ọ,+

Torí ìbínú ni mo fi kọ lù ọ́,

Àmọ́ màá fi ojúure* mi ṣàánú rẹ.+

11 Àwọn ẹnubodè rẹ máa wà ní ṣíṣí nígbà gbogbo;+

Wọn ò ní tì wọ́n ní ọ̀sán tàbí ní òru,

Láti mú ohun àmúṣọrọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè wá sọ́dọ̀ rẹ,

Àwọn ọba wọn sì máa ṣáájú.+

12 Torí orílẹ̀-èdè àti ìjọba èyíkéyìí tí kò bá sìn ọ́ máa ṣègbé,

Àwọn orílẹ̀-èdè sì máa pa run pátápátá.+

13 Ọ̀dọ̀ rẹ ni ògo Lẹ́bánónì máa wá,+

Igi júnípà, igi áàṣì àti igi sípírẹ́sì lẹ́ẹ̀kan náà,+

Láti ṣe ibi mímọ́ mi lọ́ṣọ̀ọ́;

Màá ṣe ibi tí ẹsẹ̀ mi wà lógo.+

14 Àwọn ọmọ àwọn tó fìyà jẹ ọ́ máa wá, wọ́n á sì tẹrí ba níwájú rẹ;

Gbogbo àwọn tó ń hùwà àfojúdi sí ọ gbọ́dọ̀ tẹrí ba níbi ẹsẹ̀ rẹ,

Wọ́n sì máa pè ọ́ ní ìlú Jèhófà,

Síónì Ẹni Mímọ́ Ísírẹ́lì.+

15 Dípò kí wọ́n pa ọ́ tì, kí wọ́n sì kórìíra rẹ, láìsí ẹni tó ń gbà ọ́ kọjá,+

Màá mú kí o di ohun àmúyangàn títí láé,

Orísun ayọ̀ láti ìran dé ìran.+

16 O sì máa mu wàrà àwọn orílẹ̀-èdè,+

O máa mu ọmú àwọn ọba;+

Wàá sì mọ̀ dájú pé èmi Jèhófà ni Olùgbàlà rẹ,

Alágbára Jékọ́bù sì ni Olùtúnrà rẹ.+

17 Dípò bàbà, màá mú wúrà wá,

Dípò irin, màá mú fàdákà wá

Dípò igi, bàbà

Àti dípò òkúta, irin;

Màá fi àlàáfíà ṣe àwọn alábòójútó rẹ,

Màá sì fi òdodo ṣe àwọn tó ń yan iṣẹ́ fún ọ.+

18 A ò ní gbúròó ìwà ipá mọ́ ní ilẹ̀ rẹ,

A ò sì ní gbúròó ìparun àti ìwópalẹ̀ nínú àwọn ààlà rẹ.+

O máa pe àwọn ògiri rẹ ní Ìgbàlà,+ o sì máa pe àwọn ẹnubodè rẹ ní Ìyìn.

19 Oòrùn ò ní jẹ́ ìmọ́lẹ̀ rẹ mọ́ ní ọ̀sán,

Ìmọ́lẹ̀ òṣùpá ò sì ní mọ́lẹ̀ fún ọ,

Torí Jèhófà máa di ìmọ́lẹ̀ ayérayé fún ọ,+

Ọlọ́run rẹ sì máa di ẹwà rẹ.+

20 Oòrùn rẹ ò ní wọ̀ mọ́,

Òṣùpá rẹ ò sì ní wọ̀ọ̀kùn,

Torí pé Jèhófà máa di ìmọ́lẹ̀ ayérayé fún ọ,+

Àwọn ọjọ́ ọ̀fọ̀ rẹ sì máa dópin.+

21 Gbogbo èèyàn rẹ máa jẹ́ olódodo;

Ilẹ̀ náà máa di tiwọn títí láé.

Àwọn ni èéhù ohun tí mo gbìn,

Iṣẹ́ ọwọ́ mi,+ ká lè ṣe mí lọ́ṣọ̀ọ́.+

22 Ẹni tó kéré máa di ẹgbẹ̀rún,

Ẹni kékeré sì máa di orílẹ̀-èdè alágbára.

Èmi fúnra mi, Jèhófà, máa mú kó yára kánkán ní àkókò rẹ̀.”

61 Ẹ̀mí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wà lára mi,+

Torí Jèhófà ti yàn mí kí n lè kéde ìhìn rere fún àwọn oníwà pẹ̀lẹ́.+

Ó rán mi láti di ọgbẹ́ àwọn tó ní ọgbẹ́ ọkàn,

Láti kéde òmìnira fún àwọn ẹrú,

Pé ojú àwọn ẹlẹ́wọ̀n sì máa là rekete,+

 2 Láti kéde ọdún ìtẹ́wọ́gbà* Jèhófà

Àti ọjọ́ ẹ̀san Ọlọ́run wa,+

Láti tu gbogbo àwọn tó ń ṣọ̀fọ̀ nínú,+

 3 Láti pèsè fún àwọn tó ń ṣọ̀fọ̀ torí Síónì,

Láti fún wọn ní ìwérí dípò eérú,

Òróró ayọ̀ dípò ọ̀fọ̀,

Aṣọ ìyìn dípò ìrẹ̀wẹ̀sì ọkàn.

A ó sì máa pè wọ́n ní igi ńlá òdodo,

Tí Jèhófà gbìn, kó lè ṣe é lógo.*+

 4 Wọ́n máa tún àwọn ibi tó ti pa run nígbà àtijọ́ kọ́;

Wọ́n máa kọ́ àwọn ibi tó ti dahoro nígbà àtijọ́,+

Wọ́n sì máa mú kí àwọn ìlú tó ti pa run pa dà sí bó ṣe wà tẹ́lẹ̀,+

Àwọn ibi tó ti wà ní ahoro láti ìran dé ìran.+

 5 “Àwọn àjèjì máa dúró, wọ́n sì máa tọ́jú àwọn agbo ẹran yín,

Àwọn àlejò + máa jẹ́ àgbẹ̀ yín, wọ́n á sì máa bá yín rẹ́wọ́ àjàrà.+

 6 Ní tiyín, a ó máa pè yín ní àlùfáà Jèhófà;+

Wọ́n á máa pè yín ní òjíṣẹ́ Ọlọ́run wa.

Ẹ máa jẹ ohun àmúṣọrọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè,+

Ẹ sì máa fi ògo* wọn yangàn.

 7 Dípò ìtìjú, ẹ máa ní ìpín ìlọ́po méjì,

Dípò ìdójútì, wọ́n máa kígbe ayọ̀ nítorí ìpín wọn.

Àní, ìpín ìlọ́po méjì ni wọ́n máa gbà ní ilẹ̀ wọn.+

Wọ́n á máa yọ̀ títí ayérayé.+

 8 Torí èmi Jèhófà, nífẹ̀ẹ́ ìdájọ́ òdodo;+

Mo kórìíra olè jíjà àti àìṣòdodo.+

Màá fi òótọ́ san èrè iṣẹ́ wọn fún wọn,

Màá sì bá wọn dá májẹ̀mú tó máa wà títí láé.+

 9 Wọ́n máa mọ àwọn ọmọ* wọn láàárín àwọn orílẹ̀-èdè +

Àti àtọmọdọ́mọ wọn láàárín àwọn èèyàn.

Gbogbo àwọn tó bá rí wọn máa dá wọn mọ̀,

Pé àwọn ni ọmọ* tí Jèhófà bù kún.”+

10 Màá yọ̀ gidigidi nínú Jèhófà.

Gbogbo ara mi* máa yọ̀ nínú Ọlọ́run mi.+

Torí ó ti fi ẹ̀wù ìgbàlà wọ̀ mí;+

Ó ti fi aṣọ òdodo* bò mí lára,

Bí ọkọ ìyàwó tó wé láwàní bíi ti àlùfáà+

Àti bí ìyàwó tó fi àwọn ohun ọ̀ṣọ́ rẹ̀ ṣe ara rẹ̀ lọ́ṣọ̀ọ́.

11 Torí bí ilẹ̀ ṣe ń mú irúgbìn jáde,

Tí ọgbà sì ń mú kí ohun tí wọ́n gbìn sínú rẹ̀ hù,

Bẹ́ẹ̀ ni Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ

Ṣe máa mú kí òdodo+ àti ìyìn rú jáde+ níwájú gbogbo orílẹ̀-èdè.

62 Mi ò ní dákẹ́ torí Síónì,+

Mi ò sì ní dúró jẹ́ẹ́ nítorí Jerúsálẹ́mù,

Títí òdodo rẹ̀ fi máa tàn bí iná tó mọ́lẹ̀ yòò,+

Tí ìgbàlà rẹ̀ sì máa jó bí iná ògùṣọ̀.+

 2 “Àwọn orílẹ̀-èdè máa rí òdodo rẹ, ìwọ obìnrin,+

Gbogbo àwọn ọba sì máa rí ògo rẹ.+

A sì máa fi orúkọ tuntun pè ọ́,+

Èyí tí Jèhófà máa fi ẹnu ara rẹ̀ sọ ọ́.

 3 O máa di adé ẹwà ní ọwọ́ Jèhófà,

Láwàní ọba ní àtẹ́lẹwọ́ Ọlọ́run rẹ.

 4 Wọn ò ní pè ọ́ ní obìnrin tí a pa tì mọ́,+

Wọn ò sì ní pe ilẹ̀ rẹ ní ibi tó ti dahoro mọ́.+

Àmọ́ wọ́n máa pè ọ́ ní Inú Mi Dùn sí I,+

Wọ́n sì máa pe ilẹ̀ rẹ ní Èyí Tí A Gbé Níyàwó.

Torí inú Jèhófà máa dùn sí ọ,

Ilẹ̀ rẹ sì máa dà bí èyí tí a gbé níyàwó.

 5 Torí bí ọ̀dọ́kùnrin ṣe ń gbé wúńdíá níyàwó,

Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọmọkùnrin rẹ máa gbé ọ níyàwó.

Bí ọkọ ìyàwó ṣe máa ń yọ̀ nítorí ìyàwó,

Bẹ́ẹ̀ ni Ọlọ́run rẹ máa yọ̀ nítorí rẹ.+

 6 Mo ti yan àwọn olùṣọ́ sórí àwọn ògiri rẹ, ìwọ Jerúsálẹ́mù.

Nígbà gbogbo, láti àárọ̀ ṣúlẹ̀ àti ní gbogbo òru mọ́jú, wọn ò gbọ́dọ̀ dákẹ́.

Ẹ̀yin tí ẹ̀ ń sọ̀rọ̀ Jèhófà,

Ẹ má sinmi,

 7 Ẹ má ṣe jẹ́ kó sinmi rárá, títí ó fi máa fìdí Jerúsálẹ́mù múlẹ̀ gbọn-in,

Àní, títí ó fi máa fi í ṣe ìyìn ayé.”+

 8 Jèhófà ti fi ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀, apá rẹ̀ tó lágbára, búra pé:

“Mi ò ní fi ọkà rẹ ṣe oúnjẹ fún àwọn ọ̀tá rẹ mọ́,

Àwọn àjèjì ò sì ní mu wáìnì tuntun rẹ mọ́, èyí tí o ṣiṣẹ́ kára fún.+

 9 Àmọ́ àwọn tó ń kó o jọ máa jẹ ẹ́, wọ́n sì máa yin Jèhófà;

Àwọn tó ń gbà á sì máa mu ún ní àwọn àgbàlá mímọ́ mi.”+

10 Ẹ kọjá, ẹ gba àwọn ẹnubodè kọjá.

Ẹ tún ọ̀nà ṣe fún àwọn èèyàn.+

Ẹ ṣe ọ̀nà, ẹ ṣe òpópó.

Ẹ ṣa òkúta kúrò níbẹ̀.+

Ẹ gbé àmì* sókè fún àwọn èèyàn.+

11 Ẹ wò ó! Jèhófà ti kéde títí dé àwọn ìkángun ayé pé:

“Ẹ sọ fún ọmọbìnrin Síónì pé,

‘Wò ó! Ìgbàlà rẹ ń bọ̀.+

Wò ó! Èrè rẹ̀ wà pẹ̀lú rẹ̀,

Ẹ̀san rẹ̀ sì wà níwájú rẹ̀.’”+

12 Wọ́n máa pè wọ́n ní àwọn èèyàn mímọ́, àwọn tí Jèhófà tún rà,+

A sì máa pè ọ́ ní Ẹni Tí A Wá, Ìlú Tí A Kò Pa Tì.+

63 Ta ló ń bọ̀ láti Édómù+ yìí,

Tó ń bọ̀ láti Bósírà,+ tó wọ aṣọ tí àwọ̀ rẹ̀ ń tàn yòò,*

Tó wọ aṣọ tó dáa gan-an,

Tó ń yan bọ̀ nínú agbára ńlá rẹ̀?

“Èmi ni, Ẹni tó ń fi òdodo sọ̀rọ̀,

Ẹni tó lágbára gan-an láti gbani là.”

 2 Kí ló dé tí aṣọ rẹ pọ́n,

Kí ló sì dé tí ẹ̀wù rẹ dà bíi ti ẹni tó ń tẹ àjàrà ní ibi tí wọ́n ti ń fún wáìnì?+

 3 “Èmi nìkan ni mo tẹ wáìnì nínú ọpọ́n.

Ìkankan nínú àwọn èèyàn náà ò sí lọ́dọ̀ mi.

Mò ń fi ìbínú tẹ̀ wọ́n ṣáá,

Mo sì ń fi ìrunú tẹ̀ wọ́n mọ́lẹ̀.+

Ẹ̀jẹ̀ wọn ta sára ẹ̀wù mi,

Ó sì ti yí gbogbo aṣọ mi.

 4 Torí pé ọjọ́ ẹ̀san wà lọ́kàn mi,+

Ọdún àwọn tí mo tún rà sì ti dé.

 5 Mo wò, àmọ́ kò sẹ́ni tó ṣèrànwọ́;

Ẹnu yà mí pé kò sẹ́ni tó tì mí lẹ́yìn.

Apá mi wá mú ìgbàlà* wá fún mi,+

Ìbínú mi sì tì mí lẹ́yìn.

 6 Mo fi ìbínú tẹ àwọn èèyàn mọ́lẹ̀,

Mo mú kí wọ́n mu ìrunú mi yó,+

Mo sì da ẹ̀jẹ̀ wọn sórí ilẹ̀.”

 7 Màá sọ̀rọ̀ nípa àwọn ohun tí Jèhófà ṣe torí ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀,

Àwọn iṣẹ́ Jèhófà tó yẹ ká yìn,

Torí gbogbo ohun tí Jèhófà ti ṣe fún wa,+

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ohun rere tó ti ṣe fún ilé Ísírẹ́lì,

Nínú àánú rẹ̀ àti ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ tó lágbára.

 8 Torí ó sọ pé: “Ó dájú pé èèyàn mi ni wọ́n, àwọn ọmọ tí kò ní di aláìṣòótọ́.”*+

Ó wá di Olùgbàlà wọn.+

 9 Nínú gbogbo ìdààmú wọn, ìdààmú bá òun náà.+

Ìránṣẹ́ òun fúnra rẹ̀* sì gbà wọ́n là.+

Ó tún wọn rà nínú ìfẹ́ rẹ̀ àti ìyọ́nú rẹ̀,+

Ó gbé wọn sókè, ó sì rù wọ́n ní gbogbo ìgbà àtijọ́.+

10 Àmọ́ wọ́n ṣọ̀tẹ̀ sí i,+ wọ́n sì kó ẹ̀dùn ọkàn bá ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀.+

Ó wá di ọ̀tá wọn,+

Ó sì bá wọn jà.+

11 Wọ́n rántí àwọn ìgbà àtijọ́,

Àwọn ọjọ́ Mósè ìránṣẹ́ rẹ̀:

“Ẹni tó mú wọn jáde látinú òkun dà,+ àwọn àti àwọn olùṣọ́ àgùntàn agbo ẹran rẹ̀?+

Ẹni tó fi ẹ̀mí mímọ́ Rẹ̀ sínú rẹ̀ dà,+

12 Ẹni tó mú kí apá Rẹ̀ ológo bá ọwọ́ ọ̀tún Mósè lọ,+

Ẹni tó pín omi níyà níwájú wọn,+

Kó lè ṣe orúkọ tó máa wà títí láé fún ara rẹ̀,+

13 Ẹni tó mú kí wọ́n rìn gba inú omi tó ń ru gùdù,*

Tó fi jẹ́ pé wọ́n rìn láìkọsẹ̀,

Bí ẹṣin ní ìgbèríko?*

14 Bí ìgbà tí ẹran ọ̀sìn bá ń sọ̀ kalẹ̀ lọ sí pẹ̀tẹ́lẹ̀,

Ẹ̀mí Jèhófà mú kí wọ́n sinmi.”+

Bí o ṣe darí àwọn èèyàn rẹ nìyí,

Kí o lè ṣe orúkọ tó gbayì* fún ara rẹ.+

15 Wo ilẹ̀ láti ọ̀run, kí o sì rí i

Láti ibùgbé rẹ mímọ́ àti ológo* tó ga.

Ìtara rẹ àti agbára rẹ dà,

Ìyọ́nú rẹ tó ń ru sókè*+ àti àánú rẹ dà?+

A ti fà wọ́n sẹ́yìn kúrò lọ́dọ̀ mi.

16 Torí ìwọ ni Bàbá wa;+

Bí Ábúráhámù ò tiẹ̀ mọ̀ wá,

Tí Ísírẹ́lì ò sì dá wa mọ̀,

Ìwọ Jèhófà, ni Bàbá wa.

Olùtúnrà wa látìgbà àtijọ́ ni orúkọ rẹ.+

17 Jèhófà, kí ló dé tí o gbà ká* rìn gbéregbère kúrò ní àwọn ọ̀nà rẹ?

Kí ló dé tí o gbà kí* ọkàn wa le, tí a ò fi bẹ̀rù rẹ?+

Pa dà, torí àwọn ìránṣẹ́ rẹ,

Àwọn ẹ̀yà ogún rẹ.+

18 Ó jẹ́ ti àwọn èèyàn mímọ́ rẹ fúngbà díẹ̀.

Àwọn ọ̀tá wa ti tẹ ibi mímọ́ rẹ mọ́lẹ̀.+

19 Ó pẹ́ gan-an tí a ti dà bí àwọn tí o kò ṣàkóso wọn rí,

Bí àwọn tí a ò fi orúkọ rẹ pè rí.

64 Ká ní o ti fa ọ̀run ya, tí o sì sọ̀ kalẹ̀,

Kí àwọn òkè lè mì tìtì nítorí rẹ,

 2 Bí ìgbà tí iná ran igi wíwẹ́,

Tí iná sì mú kí omi hó,

Àwọn ọ̀tá rẹ máa wá mọ orúkọ rẹ,

Àwọn orílẹ̀-èdè sì máa gbọ̀n rìrì níwájú rẹ!

 3 Nígbà tí o ṣe àwọn ohun tó ń bani lẹ́rù, tí a ò jẹ́ retí,+

O sọ̀ kalẹ̀, àwọn òkè sì mì tìtì níwájú rẹ.+

 4 Láti ìgbà àtijọ́, kò sẹ́ni tó gbọ́ tàbí tó fetí sílẹ̀,

Kò sí ojú tó rí Ọlọ́run kankan àfi ìwọ,

Tó ń gbé ìgbésẹ̀ nítorí àwọn tó ń retí rẹ̀.*+

 5 O ti bá àwọn tó ń fayọ̀ ṣe ohun tó tọ́ pàdé,+

Àwọn tó ń rántí rẹ, tí wọ́n sì ń tẹ̀ lé àwọn ọ̀nà rẹ.

Wò ó! Inú bí ọ, nígbà tí à ń ṣẹ̀ ṣáá,+

Ó pẹ́ gan-an tí a fi ṣe bẹ́ẹ̀.

Ṣé ó wá yẹ ká rígbàlà báyìí?

 6 Gbogbo wa ti dà bí aláìmọ́,

Gbogbo iṣẹ́ òdodo wa sì dà bí aṣọ tí wọ́n fi ṣe nǹkan oṣù.+

Gbogbo wa máa rọ bí ewé,

Àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa sì máa gbé wa lọ bí atẹ́gùn.

 7 Kò sẹ́ni tó ń pe orúkọ rẹ,

Kò sẹ́ni tó ń ru ara rẹ̀ sókè láti gbá ọ mú,

Torí o ti fi ojú rẹ pa mọ́ fún wa,+

O sì mú ká ṣègbé* torí* ẹ̀ṣẹ̀ wa.

 8 Àmọ́ ní báyìí, Jèhófà, ìwọ ni Bàbá wa.+

Àwa ni amọ̀, ìwọ sì ni Ẹni tó mọ wá;*+

Iṣẹ́ ọwọ́ rẹ ni gbogbo wa.

 9 Jèhófà, má ṣe bínú jù,+

Má sì rántí àwọn àṣìṣe wa títí láé.

Jọ̀ọ́, wò wá, torí èèyàn rẹ ni gbogbo wa.

10 Àwọn ìlú mímọ́ rẹ ti di aginjù.

Síónì ti di aginjù,

Jerúsálẹ́mù ti di ahoro.+

11 Ilé* wa mímọ́ àti ológo,*

Tí àwọn baba ńlá wa ti yìn ọ́,

Ni wọ́n ti dáná sun,+

Gbogbo àwọn ohun tó ṣeyebíye sí wa sì ti pa run.

12 Pẹ̀lú èyí, ṣé o ṣì máa dúró, Jèhófà?

Ṣé o ṣì máa dákẹ́ jẹ́ẹ́, tí wàá sì jẹ́ kí ìyà jẹ wá gidigidi?+

65 “Mo ti jẹ́ kí àwọn tí kò béèrè mi wá mi;

Mo ti jẹ́ kí àwọn tí kò wá mi rí mi.+

Mo sọ fún orílẹ̀-èdè tí kò pe orúkọ mi pé, ‘Èmi nìyí, èmi nìyí!’+

 2 Mo ti tẹ́ ọwọ́ mi sí àwọn alágídí láti àárọ̀ ṣúlẹ̀,+

Sí àwọn tó ń rìn ní ọ̀nà tí kò dáa,+

Tí wọ́n ń tẹ̀ lé èrò tiwọn;+

 3 Àwọn èèyàn tó ń fìgbà gbogbo ṣe ohun tó ń bí mi nínú níṣojú mi, +

Tí wọ́n ń rúbọ nínú àwọn ọgbà,+ tí wọ́n sì ń mú ẹbọ rú èéfín lórí àwọn bíríkì.

 4 Wọ́n jókòó sáàárín àwọn sàréè,+

Wọ́n sì sun àwọn ibi tó pa mọ́* mọ́jú,

Wọ́n ń jẹ ẹran ẹlẹ́dẹ̀,+

Omi àwọn nǹkan tó ń ríni lára* sì wà nínú àwọn ohun èlò wọn.+

 5 Wọ́n sọ pé, ‘Dúró sí àyè rẹ; má ṣe sún mọ́ mi,

Torí mo mọ́ jù ọ́ lọ.’*

Èéfín ni àwọn yìí nínú ihò imú mi, iná tó ń jó láti àárọ̀ ṣúlẹ̀.

 6 Wò ó! A ti kọ ọ́ níwájú mi;

Mi ò kàn ní dúró,

Àmọ́ màá san wọ́n lẹ́san,+

Màá san wọ́n lẹ́san ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́*

 7 Torí ẹ̀ṣẹ̀ wọn àti ẹ̀ṣẹ̀ àwọn baba ńlá wọn pẹ̀lú,”+ ni Jèhófà wí.

“Torí pé wọ́n ti mú ẹbọ rú èéfín lórí àwọn òkè,

Wọ́n sì ti gàn mí lórí àwọn òkè,+

Màá kọ́kọ́ díwọ̀n èrè wọn ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́.”*

 8 Ohun tí Jèhófà sọ nìyí:

“Bí ìgbà tí wọ́n rí wáìnì tuntun nínú òṣùṣù èso àjàrà,

Tí ẹnì kan wá sọ pé, ‘Má bà á jẹ́, torí ohun tó dáa* wà nínú rẹ̀,’

Bẹ́ẹ̀ ni màá ṣe nítorí àwọn ìránṣẹ́ mi;

Mi ò ní pa gbogbo wọn run.+

 9 Màá mú ọmọ* kan jáde látinú Jékọ́bù,

Màá sì mú ẹni tó máa jogún àwọn òkè mi jáde látinú Júdà;+

Àwọn àyànfẹ́ mi máa gbà á,

Àwọn ìránṣẹ́ mi á sì máa gbé níbẹ̀.+

10 Ṣárónì+ máa di ibi tí àgùntàn á ti máa jẹko,

Àfonífojì* Ákórì+ sì máa di ibi ìsinmi àwọn màlúù

Fún àwọn èèyàn mi tó ń wá mi.

11 Àmọ́ ẹ wà lára àwọn tó ń fi Jèhófà sílẹ̀,+

Àwọn tó ń gbàgbé òkè mímọ́ mi,+

Àwọn tó ń tẹ́ tábìlì fún ọlọ́run Oríire

Àti àwọn tó ń bu àdàlù wáìnì kún inú ife fún ọlọ́run Àyànmọ́.

12 Torí náà, màá yàn yín fún idà,+

Gbogbo yín sì máa tẹrí ba kí wọ́n lè pa yín,+

Torí mo pè, àmọ́ ẹ ò dáhùn,

Mo sọ̀rọ̀, àmọ́ ẹ ò fetí sílẹ̀;+

Ẹ̀ ń ṣe ohun tó burú lójú mi ṣáá,

Ẹ sì yan ohun tí inú mi ò dùn sí.”+

13 Torí náà, ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí:

“Wò ó! Àwọn ìránṣẹ́ mi máa jẹun, àmọ́ ebi máa pa ẹ̀yin.+

Wò ó! Àwọn ìránṣẹ́ mi máa mu,+ àmọ́ òùngbẹ máa gbẹ ẹ̀yin.

Wò ó! Àwọn ìránṣẹ́ mi máa yọ̀,+ àmọ́ ojú máa ti ẹ̀yin.+

14 Wò ó! Àwọn ìránṣẹ́ mi máa kígbe ayọ̀ torí pé ayọ̀ kún inú ọkàn,

Àmọ́ ẹ̀yin máa ké jáde torí ìrora ọkàn,

Ẹ sì máa pohùn réré ẹkún torí ìbànújẹ́ ọkàn.

15 Ẹ máa fi orúkọ kan sílẹ̀ tí àwọn àyànfẹ́ mi máa fi gégùn-ún,

Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sì máa pa yín níkọ̀ọ̀kan,

Àmọ́ ó máa fi orúkọ míì pe àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀;+

16 Kí Ọlọ́run òtítọ́* lè bù kún

Ẹnikẹ́ni tó bá ń wá ìbùkún fún ara rẹ̀ ní ayé,

Kí ẹnikẹ́ni tó bá sì ń búra ní ayé

Lè fi Ọlọ́run òtítọ́* búra.+

Torí àwọn wàhálà* àtijọ́ máa di ohun ìgbàgbé;

Wọ́n máa pa mọ́ kúrò ní ojú mi.+

17 Torí wò ó! Mò ń dá ọ̀run tuntun àti ayé tuntun;+

Àwọn ohun àtijọ́ ò ní wá sí ìrántí,

Wọn ò sì ní wá sí ọkàn.+

18 Torí náà, ẹ yọ̀, kí inú yín sì máa dùn títí láé torí ohun tí mò ń dá.

Torí wò ó! Mò ń dá Jerúsálẹ́mù láti mú ayọ̀ wá

Àti àwọn èèyàn rẹ̀ láti jẹ́ orísun ìdùnnú.+

19 Inú mi máa dùn nínú Jerúsálẹ́mù, màá sì yọ̀ torí àwọn èèyàn mi;+

A ò ní gbọ́ igbe ẹkún tàbí igbe ìdààmú nínú rẹ̀ mọ́.”+

20 “Kò ní sí ọmọ ọwọ́ kankan tó máa lo ọjọ́ díẹ̀ níbẹ̀ mọ́,

Kò sì ní sí àgbàlagbà kankan tí kò ní lo ọjọ́ rẹ̀ dé ẹ̀kúnrẹ́rẹ́.

Torí pé ọmọdé lásán la máa ka ẹnikẹ́ni tó bá kú ní ọgọ́rùn-ún (100) ọdún sí,

A sì máa gégùn-ún fún ẹlẹ́ṣẹ̀, bó tiẹ̀ jẹ́ ẹni ọgọ́rùn-ún (100) ọdún.*

21 Wọ́n á kọ́ ilé, wọ́n sì máa gbé inú wọn,+

Wọ́n á gbin ọgbà àjàrà, wọ́n sì máa jẹ èso wọn.+

22 Wọn ò ní kọ́lé fún ẹlòmíì gbé,

Wọn ò sì ní gbìn fún ẹlòmíì jẹ.

Torí pé ọjọ́ àwọn èèyàn mi máa dà bí ọjọ́ igi,+

Àwọn àyànfẹ́ mi sì máa gbádùn iṣẹ́ ọwọ́ wọn dé ẹ̀kúnrẹ́rẹ́.

23 Wọn ò ní ṣiṣẹ́ kára* lásán,*+

Wọn ò sì ní bímọ fún wàhálà,

Torí àwọn ni ọmọ* tí wọ́n jẹ́ àwọn tí Jèhófà bù kún+

Àti àwọn àtọmọdọ́mọ wọn pẹ̀lú wọn.+

24 Kódà kí wọ́n tó pè, màá dáhùn;

Bí wọ́n ṣe ń sọ̀rọ̀ lọ́wọ́, màá gbọ́.

25 Ìkookò àti ọ̀dọ́ àgùntàn máa jẹun pa pọ̀,

Kìnnìún máa jẹ pòròpórò bí akọ màlúù,+

Erùpẹ̀ sì ni ejò á máa jẹ.

Wọn ò ní ṣe ìpalára kankan, wọn ò sì ní fa ìparun kankan ní gbogbo òkè mímọ́ mi,”+ ni Jèhófà wí.

66 Ohun tí Jèhófà sọ nìyí:

“Ọ̀run ni ìtẹ́ mi, ayé sì ni àpótí ìtìsẹ̀ mi.+

Ilé wo wá ni ẹ lè kọ́ fún mi,+

Ibo sì ni ibi ìsinmi mi?”+

 2 “Ọwọ́ mi ni ó ṣe gbogbo nǹkan yìí,

Bí gbogbo wọn sì ṣe wà nìyí,” ni Jèhófà wí.+

“Màá wá wo ẹni yìí,

Ẹni tó rẹlẹ̀, tí ìbànújẹ́ sì bá ọkàn rẹ̀, tó ń gbọ̀n rìrì* nítorí ọ̀rọ̀ mi.+

 3 Ẹni tó ń pa akọ màlúù dà bí ẹni tó ń ṣá èèyàn balẹ̀.+

Ẹni tó ń fi àgùntàn rúbọ dà bí ẹni tó ń ṣẹ́ ọrùn ajá.+

Ẹni tó ń mú ẹ̀bùn wá dà bí ẹni tó ń fi ẹ̀jẹ̀ ẹlẹ́dẹ̀ rúbọ!+

Ẹni tó ń mú oje igi tùràrí wá láti fi ṣe ọrẹ ìrántí+ dà bí ẹni tó ń fi ọfọ̀ súre.*+

Wọ́n ti yan ọ̀nà tiwọn,

Ohun ìríra ló sì ń múnú wọn dùn.*

 4 Torí náà, màá yan ọ̀nà tí màá fi jẹ wọ́n níyà,+

Àwọn ohun tí wọ́n sì ń bẹ̀rù gan-an ni màá mú kó ṣẹlẹ̀ sí wọn.

Torí nígbà tí mo pè, kò sẹ́ni tó dáhùn;

Nígbà tí mo sọ̀rọ̀, kò sẹ́ni tó fetí sílẹ̀.+

Wọ́n ń ṣe ohun tó burú lójú mi ṣáá,

Ohun tí inú mi ò dùn sí ni wọ́n sì yàn pé àwọn fẹ́ ṣe.”+

 5 Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ Jèhófà, ẹ̀yin tí ẹ̀ ń gbọ̀n rìrì* torí ọ̀rọ̀ rẹ̀:

“Àwọn arákùnrin yín tó kórìíra yín, tí wọ́n sì ta yín nù nítorí orúkọ mi sọ pé, ‘Ká yin Jèhófà lógo!’+

Àmọ́ Ó máa fara hàn, ó sì máa mú ayọ̀ wá fún yín,

Àwọn sì ni ojú máa tì.”+

 6 À ń gbọ́ ariwo látinú ìlú, ìró kan látinú tẹ́ńpìlì!

Ìró Jèhófà ni, ó ń san ohun tó yẹ àwọn ọ̀tá rẹ̀ fún wọn.

 7 Kó tó bẹ̀rẹ̀ sí í rọbí, ó bímọ.+

Kí ìrora ìbímọ tó mú un, ó bí ọmọ ọkùnrin.

 8 Ta ló ti gbọ́ irú rẹ̀ rí?

Ta ló ti rí irú rẹ̀ rí?

Ṣé a lè bí ilẹ̀ kan ní ọjọ́ kan ni?

Àbí a lè bí gbogbo orílẹ̀-èdè kan lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo?

Síbẹ̀, gbàrà tí Síónì bẹ̀rẹ̀ sí í rọbí, ó bí àwọn ọmọkùnrin rẹ̀.

 9 “Ṣé màá mú kó rọbí, tí kò sì ní bímọ ni?” ni Jèhófà wí.

“Àbí máa mú kó bímọ, kí n wá ti ilé ọlẹ̀ rẹ̀ pa?” ni Ọlọ́run rẹ wí.

10 Ẹ bá Jerúsálẹ́mù yọ̀, kí ẹ sì jẹ́ kí inú yín dùn sí i,+ gbogbo ẹ̀yin tí ẹ nífẹ̀ẹ́ rẹ̀.+

Ẹ bá a yọ̀ gidigidi, gbogbo ẹ̀yin tí ẹ̀ ń ṣọ̀fọ̀ rẹ̀,

11 Ẹ máa mu ọmú rẹ̀ tó ń tuni nínú, ó sì máa tẹ́ yín lọ́rùn gidigidi,

Ẹ máa mu ún dáadáa, inú yín sì máa dùn sí ògo rẹ̀ tó pọ̀ rẹpẹtẹ.

12 Nítorí ohun tí Jèhófà sọ nìyí:

“Mò ń nawọ́ àlàáfíà sí i bíi ti odò+

Àti ògo àwọn orílẹ̀-èdè bí àkúnya omi.+

Ẹ máa mu ọmú, a máa gbé yín sí ẹ̀gbẹ́,

Wọ́n á sì máa bá yín ṣeré lórí orúnkún.

13 Bí ìyá ṣe ń tu ọmọ rẹ̀ nínú,

Bẹ́ẹ̀ ni màá máa tù yín nínú;+

Ẹ sì máa rí ìtùnú torí Jerúsálẹ́mù.+

14 Ẹ máa rí èyí, inú yín sì máa dùn,

Egungun yín máa yọ dáadáa bíi koríko tútù.

Àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà máa wá mọ ọwọ́* rẹ̀,

Àmọ́ ó máa dá àwọn ọ̀tá rẹ̀ lẹ́bi.”+

15 “Torí pé Jèhófà máa wá bí iná,+

Àwọn kẹ̀kẹ́ ẹṣin rẹ̀ sì dà bí ìjì líle,+

Láti fi ìbínú líle san ẹ̀san,

Kó sì fi ọwọ́ iná báni wí.+

16 Torí pé iná ni Jèhófà máa fi ṣèdájọ́,

Àní, ó máa fi idà rẹ̀ bá gbogbo ẹran ara* jà;

Àwọn tí Jèhófà pa sì máa pọ̀ rẹpẹtẹ.

17 Àwọn tó ń sọ ara wọn di mímọ́, tí wọ́n sì ń wẹ ara wọn láti wọnú àwọn ọgbà,*+ tí wọ́n ń tẹ̀ lé ẹni tó wà ní àárín, àwọn tó ń jẹ ẹran ẹlẹ́dẹ̀,+ àwọn ohun ìríra àti eku,+ gbogbo wọn jọ máa wá sí òpin wọn,” ni Jèhófà wí. 18 “Torí mo mọ iṣẹ́ wọn àti ìrònú wọn, mò ń bọ̀ wá kó èèyàn gbogbo orílẹ̀-èdè àti èdè jọ, wọ́n sì máa wá rí ògo mi.”

19 “Màá fi àmì kan sáàárín wọn, màá sì rán lára àwọn tó yè bọ́ lọ sí àwọn orílẹ̀-èdè, sí Táṣíṣì,+ Púlì àti Lúdì,+ àwọn tó ń ta ọfà, sí Túbálì àti Jáfánì,+ títí kan àwọn erékùṣù tó wà lọ́nà jíjìn, tí wọn ò tíì gbọ́ ìròyìn nípa mi, tí wọn ò sì tíì rí ògo mi; wọ́n sì máa kéde ògo mi láàárín àwọn orílẹ̀-èdè.+ 20 Wọ́n máa kó gbogbo àwọn arákùnrin yín jáde látinú gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè,+ wọ́n á fi wọ́n ṣe ẹ̀bùn fún Jèhófà, lórí ẹṣin, nínú kẹ̀kẹ́ ẹṣin, nínú kẹ̀kẹ́ tí wọ́n bo orí rẹ̀, lórí àwọn ìbaaka àti lórí àwọn ràkúnmí tó ń yára kánkán, wọ́n á kó wọn wá sórí òkè mímọ́ mi, ìyẹn Jerúsálẹ́mù,” ni Jèhófà wí, “bí ìgbà tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì fi ohun èlò tó mọ́ gbé ẹ̀bùn wọn wá sínú ilé Jèhófà.”

21 “Mo tún máa mú lára wọn láti ṣe àlùfáà, màá sì fi àwọn kan ṣe ọmọ Léfì,” ni Jèhófà wí.

22 “Bí ọ̀run tuntun àti ayé tuntun+ tí mò ń dá ṣe máa dúró níwájú mi,” ni Jèhófà wí, “bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọmọ* yín àti orúkọ yín ṣe máa dúró.”+

23 “Láti òṣùpá tuntun dé òṣùpá tuntun àti láti sábáàtì dé sábáàtì,

Gbogbo ẹran ara* máa wọlé wá tẹrí ba níwájú* mi,”+ ni Jèhófà wí.

24 “Wọ́n á jáde lọ, wọ́n á sì wo òkú àwọn tó ṣọ̀tẹ̀ sí mi;

Torí ìdin ara wọn ò ní kú,

Iná wọn ò ní kú,+

Wọ́n á sì di ohun tó ń kóni nírìíra sí gbogbo èèyàn.”*

Ó túmọ̀ sí “Ìgbàlà Jèhófà.”

Tàbí “mọ olúwa rẹ̀.”

Ní Héb., “tẹ̀ wọ́n.”

Tàbí “apálá.”

Tàbí “alákòóso.”

Tàbí “ìtọ́ni.”

Tàbí “Ọkàn mi.”

Tàbí “aláìlóbìí.”

Tàbí “bíà rẹ tí wọ́n fi wíìtì ṣe.”

Tàbí “aláìlóbìí.”

Ó jọ pé àwọn igi àti àwọn ọgbà tó jẹ mọ́ ìjọsìn òrìṣà ló ń sọ.

Ohun tó rí bí okùn tó sì lè tètè jóná.

Tàbí “Ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn.”

Tàbí “ìtọ́ni.”

Tàbí “tún nǹkan ṣe.”

Tàbí “rẹ ìgbéraga àwọn èèyàn wálẹ̀.”

Tàbí “igi óákù.”

Tàbí “rẹ ìgbéraga àwọn èèyàn wálẹ̀.”

Àwọn ẹranko kéékèèké afọ́mọlọ́mú tó ń jẹ nǹkan run.

Tàbí “tí èémí rẹ̀ wà nínú ihò imú rẹ̀.”

Tàbí “Àwọn tí èrò wọn ò dúró sójú kan.”

Tàbí “Mi ò ní wò ọ́ sàn.”

Ní Héb., “ní ojú ògo rẹ̀.”

Tàbí “Ọkàn wọn.”

Ní Héb., “Wọ́n máa jẹ èso iṣẹ́ ọwọ́ wọn.”

Ní Héb., “Tí wọ́n ń na ọrùn (ọ̀fun) síwájú.”

Tàbí “ohun ọ̀ṣọ́ tí wọ́n ń so mọ́ ẹ̀gbà ọrùn.”

Tàbí “ìborùn.”

Ní Héb., “Àwọn ilé ọkàn.”

Tàbí “àwọn karawun tó ń dún tí wọ́n fi ṣe ọ̀ṣọ́.”

Tàbí “àwọ̀tẹ́lẹ̀.”

Ní Héb., “aṣọ àpò ìdọ̀họ.”

Ìyẹn, ìtìjú tó máa ń bá àwọn tí kò lọ́kọ àtàwọn tí kò bímọ.

Ní Héb., “ìgbẹ́.”

Tàbí “ìmúkúrò.”

Tàbí “àwọsánmà.”

Tàbí “ìkùukùu.”

Tàbí “ohun ọ̀gbìn.”

Wo Àfikún B14.

Ìyẹn, ilẹ̀ tí 20 màlúù tí wọ́n so pọ̀ ní méjì-méjì lè túlẹ̀ rẹ̀ ní ọjọ́ kan.

Wo Àfikún B14.

Wo Àfikún B14.

Tàbí “Ṣìọ́ọ̀lù,” ìyẹn ibojì aráyé. Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.

Tàbí “ọkàn.”

Tàbí “àwọn èèyàn rẹ̀ pàtàkì.”

Tàbí “Ìdájọ́ òdodo.”

Tàbí “ìpinnu (ìmọ̀ràn) Ẹni Mímọ́ Ísírẹ́lì.”

Tàbí “ìtọ́ni.”

Tàbí “gbé òpó sókè láti ṣe àmì.”

Tàbí “Wọ́n sì ti fẹ́ tafà.”

Tàbí “ọmọ kìnnìún tó tó ọdẹ ṣe (onígọ̀gọ̀).”

Tàbí “àwọsánmà.”

Ní Héb., “Ó.”

Ní Héb., “Ohùn ẹni tó ń sọ̀rọ̀.”

Ní Héb., “A ti pa mí lẹ́nu mọ́.”

Tàbí “igi óákù.”

Tàbí “ọmọ.”

Tàbí kó jẹ́, “wọn kò.”

Ó túmọ̀ sí “Àṣẹ́kù Nìkan Ló Máa Pa Dà.”

Tàbí kó jẹ́, “dẹ́rù bà á.”

Tàbí “ká lu ògiri rẹ̀.” Ní Héb., “ká là á.”

Tàbí “Ṣìọ́ọ̀lù,” ìyẹn ibojì aráyé. Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.

Tàbí “Omidan náà.”

Ó túmọ̀ sí “Ọlọ́run Wà Pẹ̀lú Wa.”

Ìyẹn, odò Yúfírétì.

Ní Héb., “kálámù ẹni kíkú.”

Ó ṣeé ṣe kó túmọ̀ sí “Yára Sún Mọ́ Ẹrù Ogun, Tètè Lọ Síbi Ẹrù Ogun.”

Tàbí “jẹ́rìí sí i; kọ̀wé sí i.”

Ìyẹn, ìyàwó Àìsáyà.

Ní Héb., “sún mọ́ wòlíì obìnrin náà.”

Ṣílóà ni ibi tí omi ń gbà kọjá.

Ìyẹn, odò Yúfírétì.

Wo Ais 7:14.

Tàbí “Ẹ dira.”

Lédè Hébérù, Ìmánúẹ́lì túmọ̀ sí “Ọlọ́run wà pẹ̀lú wa.” Wo Ais 7:14; 8:8.

Tàbí “àkọsílẹ̀ tí wọ́n jẹ́rìí sí.”

Tàbí “ìtọ́ni.”

Tàbí “fojú sọ́nà fún.”

Tàbí “àkọsílẹ̀ tí wọ́n fọwọ́ sí.”

Ní Héb., “ìmọ́lẹ̀ àárọ̀.”

Tàbí “Ìjọba; Ìṣàkóso ọmọ aládé.”

Tàbí “Ìjọba; Ìṣàkóso ọmọ aládé.”

Ní Héb., “láti ẹ̀yìn.”

Tàbí kó jẹ́, “imọ̀ ọ̀pẹ àti koríko etí omi.”

Tàbí “aláìlóbìí.”

Tàbí “aláìlóbìí.”

Tàbí “ìyà.”

Tàbí “ògo.”

Ní Héb., “Mo.”

Tàbí “láti ọkàn dé ẹran ara.”

Tàbí “Ìyà.”

Tàbí “àáké.”

Tàbí “Ó máa fi òdodo dá ẹjọ́ àwọn ẹni rírẹlẹ̀.”

Tàbí “ẹ̀mí.”

Tàbí “ọmọ kìnnìún tó tó ọdẹ ṣe (onígọ̀gọ̀).”

Tàbí kó jẹ́, “Ọmọ màlúù àti kìnnìún á jọ máa jẹun.”

Tàbí “òpó tí a fi ṣe àmì.”

Tàbí “Àwọn orílẹ̀-èdè máa wá a.”

Ìyẹn, Babilóníà.

Tàbí “òpó tí a fi ṣe àmì.”

Ní Héb., “èjìká.”

Tàbí “Wọ́n máa mú kí agbára wọn dé.”

Tàbí kó jẹ́, “gbẹ.”

Ní Héb., “pín ahọ́n òkun Íjíbítì.”

Ìyẹn, odò Yúfírétì.

Tàbí “ẹ̀mí.”

Tàbí kó jẹ́, “pín in sí ọ̀gbàrá méje.”

“Jáà” ni ìkékúrú Jèhófà.

Tàbí “kọrin sí.”

Ní Héb., “ìwọ obìnrin,” àwọn èèyàn náà lápapọ̀ ló ń fi wé obìnrin kan.

Tàbí “òpó kan láti fi ṣe àmì.”

Ní Héb., “tí mo sọ di mímọ́.”

Ní Héb., “àti àwọn Késílì wọn,” ó ṣeé ṣe kó jẹ́ Óríónì àtàwọn àgbájọ ìràwọ̀ tó yí i ká ló ń tọ́ka sí.

Tàbí “lọ́ṣọ̀ọ́.”

Tàbí kó jẹ́, “Àwọn ẹ̀mí èṣù tó rí bí ewúrẹ́.”

Tàbí “akátá.”

Tàbí “fún wọn ní ìsinmi.”

Tàbí “sọ̀rọ̀ ẹ̀gàn.”

Tàbí “Ṣìọ́ọ̀lù,” ìyẹn ibojì aráyé. Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.

Tàbí “ti sọ di aláìlágbára.”

Ní Héb., “àwọn òbúkọ ayé.”

Tàbí “Ṣìọ́ọ̀lù,” ìyẹn ibojì aráyé. Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.

Tàbí “ìkùukùu.”

Tàbí “Ṣìọ́ọ̀lù,” ìyẹn ibojì aráyé. Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.

Ní Héb., “ilé.”

Tàbí “ẹ̀ka.”

Ní Héb., “Ìmọ̀ràn tí a gbà.”

Tàbí “tó ṣe tán láti kọ lu.”

Tàbí “ejò olóró tó ń yára kánkán.”

Tàbí “Tẹ́ńpìlì.”

Ní Héb., “aṣọ àpò ìdọ̀họ.”

Tàbí “Ọkàn rẹ̀.”

Tàbí “àwọn ẹ̀ka rẹ̀ tí èso àjàrà pupa kún ara rẹ̀ fọ́fọ́.”

Tàbí kó jẹ́ “Torí pé wọ́n ti ń kígbe ogun sórí èso ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn rẹ àti ìkórè rẹ.”

Tàbí “tí wọ́n fara balẹ̀ kà bíi ti alágbàṣe”; ìyẹn, ní ọdún mẹ́ta géérégé.

Ní Héb., “àwọn ọmọkùnrin Ísírẹ́lì.”

Ní Héb., “Ọ̀rá ẹran ara rẹ̀.”

Ó túmọ̀ sí ṣíṣà lára irè oko tí wọ́n bá fi sílẹ̀.

Tàbí “Pẹ̀tẹ́lẹ̀.”

Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.

Tàbí “tó wuni.”

Tàbí “ọlọ́run àjèjì.”

Ìyẹn, èèpo fúlẹ́fúlẹ́ ara ọkà.

Tàbí “ewéko gbígbẹ tí atẹ́gùn ń gbé kiri.”

Ní Héb., “tí a fà sókè, tí a sì bó lára.”

Tàbí “tó lókun dáadáa, tó sì ń tẹni mọ́lẹ̀.”

Tàbí “òpó tí wọ́n fi ṣe àmì.”

Tàbí kó jẹ́, “wò láti.”

Tàbí “àwọsánmà.”

Ní Héb., “tí a fà sókè, tí a sì bó lára.”

Tàbí “tó lókun dáadáa, tó sì ń tẹni mọ́lẹ̀.”

Ìyẹn, koríko etí omi.

Tàbí “ni ọkàn wọn máa gbọgbẹ́.”

Tàbí “Mémúfísì.”

Tàbí kó jẹ́, “imọ̀ ọ̀pẹ tàbí koríko etí omi.”

Tàbí “ọ̀gágun.”

Ní Héb., “aṣọ àpò ìdọ̀họ.”

Tàbí “pẹ̀lú aṣọ jáńpé lára.”

Tàbí “ojú máa ti Íjíbítì.”

Tàbí “tí ẹwà rẹ̀ wù wọ́n.”

Ó jọ pé agbègbè Babilóníà àtijọ́ ló ń sọ.

Ní Héb., “ìrora fi kún ìbàdí mi.”

Tàbí “fi òróró sí.”

Ní Héb., “Ọmọkùnrin ibi ìpakà mi.”

Ó túmọ̀ sí “Ìpanumọ́.”

Tàbí “tí wọ́n fara balẹ̀ kà bíi ti alágbàṣe”; ìyẹn, ní ọdún kan géérégé.

Ó ṣe kedere pé Jerúsálẹ́mù ló ń sọ.

Àkànlò èdè tó ṣeé ṣe kí wọ́n máa lò láti káàánú ẹnì kan tàbí bá a kẹ́dùn.

Tàbí “agẹṣin.”

Tàbí “ṣètò.”

Tàbí “pẹ̀tẹ́lẹ̀.”

Tàbí “agẹṣin.”

Tàbí “ohun tí wọ́n fi dáàbò bo.”

Ní Héb., “aṣọ àpò ìdọ̀họ.”

Tàbí “ààfin.”

Ní Héb., “ilé.”

Tàbí “agbára.”

Ní Héb., “ìwúwo.”

Tàbí “èéhù.”

Ní Héb., “Irúgbìn.”

Ìyẹn, odò tó ya láti ara odò Náílì.

Ní Héb., “àwọn wúńdíá.”

Tàbí kó jẹ́, “ibi tí ọkọ̀ òkun ń gúnlẹ̀ sí.”

Ní Héb., “àwọn ọjọ́.”

Tàbí “ayé.”

Tàbí “Ó ń yí ojú rẹ̀ po.”

Tàbí kó jẹ́, “gbẹ táútáú.”

Tàbí “májẹ̀mú àtijọ́.”

Tàbí kó jẹ́, “gbẹ táútáú.”

Ó túmọ̀ sí ṣíṣà lára irè oko tí wọ́n bá fi sílẹ̀.

Tàbí “ìwọ̀ oòrùn.”

Tàbí “ní ìlà oòrùn.”

Tàbí “Ẹ ṣe Olódodo lọ́ṣọ̀ọ́!”

Ní Héb., “níwájú àwọn àgbààgbà rẹ̀.”

Tàbí “Àwọn ìmọ̀ràn.”

Tàbí “àwọsánmà.”

Tàbí “wáìnì tó wà lórí gẹ̀dẹ̀gẹ́dẹ̀.”

Ní Héb., “gbé ohun tó ń bo gbogbo èèyàn mì.”

Tàbí “ìbòjú.”

Tàbí “mú ikú kúrò.”

Tàbí kó jẹ́, “àwọn tí wọn kì í yí èrò ọkàn wọn pa dà.”

“Jáà” ni ìkékúrú Jèhófà.

Tàbí “tẹ́jú.”

Tàbí “wu ọkàn wa.”

Ìyẹn ni pé, ká máa rántí Ọlọ́run àti orúkọ rẹ̀, ká jẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ ọ́n.

Tàbí “ara.”

Tàbí “ìṣòtítọ́.”

Tàbí “ti sọ wọ́n di aláìlágbára.”

Ní Héb., “Òkú tó jẹ́ tèmi.”

Tàbí kó jẹ́, “ìrì àwọn ewéko (málò).”

Tàbí “ti sọ di aláìlágbára.”

Tàbí “máa bí àwọn tí ikú ti sọ di aláìlágbára.”

Tàbí “ìbáwí.”

Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.

Ó jọ pé Ísírẹ́lì ló ń tọ́ka sí, ó pè é ní obìnrin, ó sì fi wé ọgbà àjàrà.

Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.

Ìyẹn, odò Yúfírétì.

Ó jọ pé Samáríà tó jẹ́ olú ìlú ló ń sọ.

Tàbí “ìyangàn.”

Tàbí “ìyangàn.”

Tàbí “Okùn ìdíwọ̀n lé okùn ìdíwọ̀n, okùn ìdíwọ̀n lé okùn ìdíwọ̀n.”

Ní Héb., “àwọn tí ètè wọn ń kólòlò.”

Tàbí “Okùn ìdíwọ̀n lé okùn ìdíwọ̀n, okùn ìdíwọ̀n lé okùn ìdíwọ̀n.”

Tàbí “Ṣìọ́ọ̀lù,” ìyẹn ibojì aráyé. Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.

Tàbí kó jẹ́, “A sì ti fìdí ìran kan múlẹ̀ pẹ̀lú Isà Òkú.”

Tàbí “okùn tí a fi ń mọ̀ bóyá nǹkan gún régé.”

Tàbí “Ṣìọ́ọ̀lù,” ìyẹn ibojì aráyé. Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.

Tàbí kó jẹ́, “Tó bá ti yé wọn, ìbẹ̀rù máa bò wọ́n.”

Tàbí “pẹ̀tẹ́lẹ̀.”

Tàbí “gbogbo ayé.”

Tàbí “wíìtì.”

Tàbí “bá a wí.”

Tàbí “ète.”

Tàbí “Tí ọgbọ́n rẹ̀ tó gbéṣẹ́ sì ga lọ́lá.”

Ó ṣeé ṣe kó túmọ̀ sí “Ibi Ìdáná Pẹpẹ Ọlọ́run,” ó jọ pé Jerúsálẹ́mù ló ń tọ́ka sí.

Ní Héb., “àjèjì.”

Ìyẹn, èèpo fúlẹ́fúlẹ́ ara ọkà.

Tàbí “tí ọkàn rẹ̀ sì ṣófo.”

Tàbí “tí ọkàn rẹ̀ sì gbẹ.”

Tàbí “ìmọ̀ràn wọn.”

Tàbí “Ẹ wo bí ẹ ṣe gbé nǹkan gbòdì.”

Ní Héb., “ẹni tó ń báni wí.”

Ìyẹn, nítorí ìtìjú àti ìjákulẹ̀.

Ní Héb., “ṣìnà nínú ẹ̀mí.”

Ní Héb., “ta ohun tí wọ́n fi rúbọ sílẹ̀,” ó ṣe kedere pé ṣíṣe àdéhùn ló ń sọ.

Tàbí “láìgbọ́ tẹnu mi.”

Ní Héb., “sínú ibi ààbò Fáráò.”

Tàbí “ejò olóró tó ń yára kánkán.”

Tàbí “ìtọ́ni.”

Ní Héb., “tó dùn-ún gbọ́.”

Tàbí kó jẹ́, “kòtò omi.”

Tàbí “ń fojú sọ́nà.”

Tàbí “ń fojú sọ́nà fún un.”

Tàbí “ère dídà.”

Tàbí kó jẹ́, “ẹ sì máa pè wọ́n ní ohun ìdọ̀tí.”

Ní Héb., “ó sì máa lóròóró dáadáa.”

Tàbí “egungun àwọn èèyàn rẹ̀ tó fọ́.”

Tàbí “ìkùukùu.”

Tàbí “Èémí.”

Ní Héb., “ajọ̀ àìníláárí.”

Tàbí “sọ ara yín di mímọ́.”

Tàbí “tó ń tẹ̀ lé ìró fèrè bó ṣe ń rìn.”

“Tófétì” tí wọ́n lò níbí dúró fún ibi tí wọ́n ti ń dáná sun nǹkan, èyí tó ṣàpẹẹrẹ ìparun.

Tàbí “àwọn agẹṣin.”

Tàbí “ọmọ kìnnìún tó tó ọdẹ ṣe (onígọ̀gọ̀).”

Tàbí “iná.”

Tàbí “ibi ààbò.”

Tàbí “ìlùmọ́.”

Tàbí “hùwà àfojúdi.”

Tàbí “ọkàn ẹni tí ebi ń pa.”

Tàbí “tó dáa.”

Ní Héb., “aṣọ àpò ìdọ̀họ.”

Tàbí “tú akọ màlúù àti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ sílẹ̀.”

Tàbí “agbára.”

Ọ̀tá ló ń tọ́ka sí.

Tàbí kó jẹ́, “gbẹ dà nù.”

Tàbí “Ibi gíga rẹ̀ tó láàbò.”

Tàbí “ṣàṣàrò nípa.”

Tàbí “owó òde.”

Ní Héb., “jinlẹ̀.”

Tàbí “olùgbé kankan.”

Tàbí “Ẹ̀jẹ̀ wọn á máa ṣàn lórí àwọn òkè.”

Ó ṣe kedere pé Bósírà, olú ìlú Édómù ló ń tọ́ka sí.

Ní Héb., “Àti àwọn òkúta ahoro.”

Tàbí “akátá.”

Tàbí kó jẹ́, “Ẹ̀mí èṣù tó rí bí ewúrẹ́.”

Ní Héb., “fi okùn ìdíwọ̀n pín in fún wọn.”

Ìyẹn, koríko etí omi.

Tàbí “akátá.”

Tàbí “olórí agbọ́tí.”

Tàbí “ààfin.”

Ìyẹn, koríko etí omi.

Tàbí “Síríà.”

Ní Héb., “Ẹ wá ìbùkún lọ́dọ̀ mi, kí ẹ sì jáde wá bá mi.”

Tàbí “ààfin.”

Ní Héb., “aṣọ àpò ìdọ̀họ.”

Tàbí “ààfin.”

Tàbí “èébú.”

Ní Héb., “àwọn ọmọ ti dé ẹnu ilé ọmọ.”

Tàbí “ìránṣẹ́.”

Ní Héb., “ẹ̀mí kan sínú rẹ̀.”

Ní Héb., “ẹ.”

Tàbí kó jẹ́, “láàárín.”

Tàbí “ipa odò Náílì.”

Ní Héb., “ni mo ti ṣe é.”

Tàbí “mọ ọ́n.”

Ìyẹn, Hẹsikáyà.

Tàbí “hóró ọkà tó dà sílẹ̀ tó lalẹ̀ hù.”

Tàbí “tẹ́ńpìlì.”

Ní Héb., “àwọn ọjọ́.”

Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé àwọn àtẹ̀gùn yìí ni wọ́n fi ń ka àkókò bíi ti aago òjìji oòrùn.

Tàbí “Ewì.”

Tàbí “Ṣìọ́ọ̀lù,” ìyẹn ibojì aráyé. Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.

“Jáà” ni ìkékúrú Jèhófà.

Tàbí kó jẹ́, “ẹyẹ òfú.”

Ní Héb., “Ṣe onídùúró mi.”

Tàbí “tìrònútìrònú.”

Tàbí “ọkàn mi tó gbọgbẹ́.”

Ìyẹn, ọ̀rọ̀ Ọlọ́run àtàwọn ohun tí Ọlọ́run ń ṣe.

Tàbí “ọkàn mi.”

Tàbí “mú gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ mi kúrò níwájú rẹ.”

Tàbí “Ṣìọ́ọ̀lù,” ìyẹn ibojì aráyé. Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.

Ní Héb., “yọ̀ nítorí wọn.”

Tàbí “ààfin.”

Tàbí “ààfin.”

Tàbí “ààfin.”

Tàbí “ààfin.”

Tàbí “òtítọ́.”

Ní Héb., “ní àwọn ọjọ́.”

Tàbí “Ẹ sọ ọ̀rọ̀ ìtùnú fún Jerúsálẹ́mù.”

Tàbí “ìlọ́po méjì.”

Tàbí “Ẹ múra ọ̀nà Jèhófà sílẹ̀!”

Tàbí “Gbogbo èèyàn.”

Tàbí “gbogbo èèyàn.”

Tàbí “ẹ̀mí.”

Tàbí “darí.”

Àlàfo tó wà láàárín orí àtàǹpàkò àti ìka tó kéré jù téèyàn bá yàka. Wo Àfikún B14.

Tàbí “díwọ̀n.”

Tàbí kó jẹ́, “lóye.”

Tàbí “kò lè mú igi ìdáná tó máa tó jáde.”

Tàbí “ère dídà.”

Tàbí “òbìrí.”

Tàbí “àwọn alákòóso.”

Tàbí “Òye rẹ̀ kò ṣeé lóye.”

Tàbí “tí kò ní agbára (okun) láti ṣiṣẹ́.”

Tàbí “Ẹ dákẹ́ níwájú mi.”

Tàbí “láti ìlà oòrùn.”

Ìyẹn, láti sìn Ín.

Ìyẹn, hámà ńlá tí àwọn alágbẹ̀dẹ máa ń lò.

Ní Héb., “Èso.”

Ìyẹn, ẹni tó rẹlẹ̀ tí kò sì lè gbèjà ara rẹ̀.

Ìyẹn, èèpo fúlẹ́fúlẹ́ ara ọkà.

Ìyẹn, koríko etí omi.

Ní Héb., “àkọ́kọ́.”

Tàbí “fọkàn sí i.”

Tàbí “láti ìlà oòrùn.”

Tàbí “ìjòyè.”

Tàbí “ohun tí kò sí rárá.”

Tàbí “ère dídà.”

Tàbí “ọkàn mi.”

Ìyẹn, koríko etí omi.

Tàbí “ìtọ́ni.”

Tàbí “Èmi kì í bá ẹnì kankan pín ògo mi.”

Tàbí “ilẹ̀ etíkun.”

Ìyẹn, koríko etí omi.

Tàbí “ère dídà.”

Tàbí “ìtọ́ni.”

Tàbí “ìtọ́ni.”

Tàbí “ọkàn.”

Ní Héb., “èso.”

Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ àwọn ohun tó máa kọ́kọ́ ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú.

Tàbí “gbẹ́kẹ̀ lé mi.”

Tàbí “akátá.”

Esùsú tó ń ta sánsán.

Tàbí “ìwà ọ̀tẹ̀.”

Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ àwọn olùkọ́ Òfin ló ń tọ́ka sí.

Tàbí “láti ìgbà tí wọ́n ti bí ọ.”

Ó túmọ̀ sí “Adúróṣinṣin,” orúkọ oyè tí wọ́n fún Ísírẹ́lì.

Tàbí “ilẹ̀.”

Ní Héb., “èso.”

Ìyẹn, àwọn ère náà.

Tàbí “ère dídà.”

Tàbí “ohun èlò tí wọ́n fi ń gbẹ́ nǹkan.”

Tàbí “sí ojúbọ.”

Tàbí “igi óákù.”

Tàbí “ìtì igi gbígbẹ.”

Tàbí “ọkàn.”

Tàbí “àwọsánmà.”

Tàbí “àwọn wòlíì èké.”

Ní Héb., “tú àmùrè ìbàdí.”

Ní Héb., “dì ọ́ lámùrè gírígírí.”

Tàbí “Láti ìlà oòrùn dé ìwọ̀ oòrùn.”

Tàbí “Ẹni tó dá a.”

Tàbí “bá Aṣẹ̀dá rẹ̀ jiyàn.”

Tàbí “Ẹni tó mọ ọ́n.”

Tàbí kó jẹ́, “Àbí ó yẹ kí amọ̀ sọ pé: ‘Iṣẹ́ rẹ ò ní ọwọ́’?”

Tàbí “Kí lò ń rọbí rẹ̀?”

Tàbí kó jẹ́, “Àwọn alágbàṣe.”

Tàbí kó jẹ́, “àwọn oníṣòwò.”

Tàbí kó jẹ́, “dá a pé kó ṣófo.”

Ní Héb., “èso.”

Tàbí “wá mi lórí òfo.”

Ní Héb., “èso.”

Ìyẹn, àwọn òrìṣà tí wọ́n kó sẹ́yìn àwọn ẹranko.

Tàbí “Ọkàn wọn.”

Ní Héb., “forí balẹ̀ fún un.”

Ní Héb., “àkọ́kọ́.”

Tàbí “Olú Ọ̀run.”

Tàbí “Ohun tí mo ní lọ́kàn; Ìmọ̀ràn mi.”

Tàbí “ìlà oòrùn.”

Tàbí “ohun tí mo ní lọ́kàn; ìmọ̀ràn mi.”

Ní Héb., “ọlọ́kàn tó yi.”

Tàbí kó jẹ́, “mi ò sì ní ṣàánú ẹnikẹ́ni.”

Tàbí “Ọbabìnrin.”

Tàbí “Ọbabìnrin.”

Tàbí kó jẹ́, “Láìka.”

Tàbí “O ò sì ní lè sa oògùn sí i.”

Tàbí kó jẹ́, “Àwọn tó ń pín ọ̀run; Àwọn awòràwọ̀.”

Tàbí “ọkàn.”

Ní Héb., “kálukú lọ sí agbègbè rẹ̀.”

Tàbí kó jẹ́, “ṣẹ̀ wá láti.”

Ní Héb., “àkọ́kọ́.”

Tàbí “ère dídà.”

Tàbí “yẹ̀ ọ́ wò.” Tàbí kó jẹ́, “yàn ọ́.”

Tàbí “Èmi kì í bá ẹnì kankan pín ògo mi.”

Tàbí “pẹ̀lú.”

Tàbí “fún àǹfààní ara rẹ.”

Ní Héb., “èso.”

Ní Héb., “látinú oyún.”

Tàbí “Jèhófà máa dá ẹjọ́ mi bó ṣe tọ́.”

Tàbí “Owó iṣẹ́.”

Tàbí “kórìíra nínú ọkàn.”

Tàbí “ìtẹ́wọ́gbà.”

Tàbí kó jẹ́, “Orí gbogbo òkè tí nǹkan kan ò ti hù.”

Tàbí “òpó tí mo fi ṣe àmì.”

Ní Héb., “Wọ́n máa gbé àwọn ọmọkùnrin rẹ sí àyà wọn.”

Ní Héb., “Gbogbo ẹran ara.”

Ní Héb., “aṣọ àpò ìdọ̀họ.”

Tàbí “ahọ́n tí a kọ́ dáadáa.”

Ní Héb., “fi ọ̀rọ̀.”

Tàbí kó jẹ́, “fún ẹni tó ti rẹ̀ lókun.”

Tàbí “àwọn tó fa irùngbọ̀n tu.”

Tàbí “bá mi fà á.”

Tàbí “dojú kọ ara wa.”

Tàbí “Kòkòrò.”

Tàbí “gbára lé.”

Tàbí “bí yín pẹ̀lú ìrora ìbímọ.”

Tàbí “agbára.”

Tàbí “ò sì ní fọ́ túútúú.”

Tàbí “ìtọ́ni.”

Tàbí “kòkòrò.”

Tàbí kó jẹ́, “Kòkòrò mùkúlú.”

Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.

Ní Héb., “wà lórí wọn.”

Tàbí “ẹni tó sé ọ mọ́.”

Ní Héb., “ìkóríta.”

Tàbí “ọkàn rẹ.”

Tàbí “kọlà.”

Tàbí “lójúkojú.”

Tàbí “ṣẹ́gun.”

Tàbí “kò ní lè sọ̀rọ̀.”

Tàbí kó jẹ́, “ohun tí a gbọ́.”

Ọ̀rọ̀ náà “rẹ̀” lè tọ́ka sí ẹnikẹ́ni tọ́rọ̀ ṣojú ẹ̀ tàbí Ọlọ́run.

Tàbí “ìrísí rẹ̀ kò ṣàrà ọ̀tọ̀ débi pé ó máa wù wá.”

Ní Héb., “tí a pète fún ìrora.”

Tàbí kó jẹ́, “Ó dà bí ẹni tí àwọn èèyàn ń gbójú kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀.”

Tàbí “ìyà.”

Tàbí “bí ìgbésí ayé rẹ̀ ṣe rí?”

Tàbí “Wọ́n pa á.”

Tàbí “Ẹnì kan máa fún un ní ibi ìsìnkú.”

Ní Héb., “ọkùnrin ọlọ́rọ̀.”

Tàbí “kò hùwà ipá kankan.”

Tàbí “Àmọ́ inú Jèhófà dùn sí i.”

Tàbí “ọkàn.”

Ní Héb., “èso.”

Tàbí “Ìfẹ́ Jèhófà; Ohun tó múnú Jèhófà dùn.”

Tàbí “ìdààmú ọkàn.”

Tàbí “ọkàn.”

Ní Héb., “àwọn ọmọkùnrin.”

Tàbí “ọ̀gá.”

Tàbí “ọ̀gá.”

Ní Héb., “tí ẹ̀mí rẹ̀ sì gbọgbẹ́.”

Tàbí “òkúta iná.”

Ní Héb., “àwọn ọmọkùnrin.”

Ní Héb., “àwọn ọmọkùnrin.”

Tàbí “Ohun àjogúnbá.”

Tàbí “owó tí ẹ ṣiṣẹ́ kára fún.”

Ní Héb., “Ọ̀rá.”

Tàbí “ọkàn yín yọ̀.”

Tàbí “ọkàn yín.”

Tàbí “tó ṣeé gbọ́kàn lé; tó ṣeé gbára lé.”

Ní Héb., “lọ́nà títóbi.”

Tàbí “máa já sí.”

Tàbí “tó bá jẹ́ ìfẹ́ mi.”

Tàbí “ṣe orúkọ fún Jèhófà.”

Tàbí “tó ní ọkàn tó le.”

Ìyẹn ni pé, wọ́n kú.

Tàbí kó jẹ́, “Kúrò lọ́wọ́.”

Ìyẹn, nínú sàréè.

Tàbí “Ṣé kí n fi àwọn nǹkan yìí tu ara mi nínú ni?”

Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ ìjọsìn òrìṣà ló ń sọ.

Tàbí kó jẹ́, “ọba.”

Tàbí “Ṣìọ́ọ̀lù,” ìyẹn ibojì aráyé. Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.

Ní Héb., “tí kò fi rẹ̀ ọ́.”

Tàbí “fi ọ̀rọ̀ pa mọ́?”

Tàbí “Tó ń gbé.”

Tàbí “Màá sì fi ìtùnú san àsandípò fún òun àti àwọn èèyàn rẹ̀.”

Tàbí “ọkàn.”

Tàbí “ìdùnnú.”

Tàbí “ọkàn.”

Ní Héb., “aṣọ àpò ìdọ̀họ.”

Tàbí “ọkàn ìwọ fúnra rẹ.”

Tàbí “àwọn ọkàn.”

Tàbí “ọkàn rẹ.”

Ní Héb., “ẹni tó ń dí àlàfo.”

Ní Héb., “Tí o bá yí ẹsẹ̀ rẹ pa dà, tí o kò wá.”

Tàbí “àwọn ohun tó ń múnú rẹ dùn.”

Tàbí “gbádùn.”

Ní Héb., “wúwo.”

Tàbí “Òfìfo.”

Tàbí “ìṣòtítọ́.”

Tàbí “Ìṣòtítọ́.”

Ní Héb., “ó sì burú ní ojú rẹ̀.”

Tàbí “mú kó ṣẹ́gun.”

Tàbí “ìṣẹ́gun.”

Tàbí “aṣọ àwọ̀lékè tí kò lápá.”

Ní Héb., “èso.”

Ní Héb., “èso àwọn èso rẹ.”

Tàbí “ìmọ́lẹ̀ àárọ̀ rẹ.”

Ní Héb., “bò ọ́.”

Tàbí “ilé ẹwà mi.”

Tàbí “àlàfo ilé ẹyẹ.”

Tàbí “ló wà bíi ti àkọ́kọ́.”

Tàbí “ṣe ọ́ lọ́ṣọ̀ọ́.”

Tàbí “ìtẹ́wọ́gbà.”

Tàbí “ojúure.”

Tàbí “kó lè bu ẹwà kún un.”

Tàbí “ọrọ̀.”

Ní Héb., “èso.”

Ní Héb., “èso.”

Tàbí “Ọkàn mi.”

Tàbí “aṣọ àwọ̀lékè òdodo tí kò lápá.”

Tàbí “òpó tí a fi ṣe àmì.”

Tàbí kó jẹ́, “aṣọ rẹ̀ pọ́n yòò.”

Tàbí “ìṣẹ́gun.”

Tàbí “já sí èké.”

Tàbí “Áńgẹ́lì iwájú rẹ̀.”

Tàbí “ibú omi.”

Tàbí “nínú aginjù?”

Tàbí “tó lẹ́wà.”

Tàbí “ẹlẹ́wà.”

Ní Héb., “Inú rẹ lọ́hùn-ún tó ń ru sókè.”

Tàbí “mú ká.”

Ní Héb., “mú kí.”

Tàbí “tó ń fi sùúrù dúró dè é.”

Ní Héb., “yọ́.”

Ní Héb., “látọwọ́.”

Tàbí “Ẹni tó dá wa; Amọ̀kòkò.”

Tàbí “Tẹ́ńpìlì.”

Tàbí “ẹlẹ́wà.”

Tàbí kó jẹ́, “àwọn ahéré ìṣọ́.”

Tàbí “aláìmọ́.”

Tàbí kó jẹ́, “Torí màá kó ìjẹ́mímọ́ mi ràn ọ́.”

Ní Héb., “sínú àyà wọn.”

Ní Héb., “sínú àyà wọn.”

Ní Héb., “ìbùkún.”

Ní Héb., “èso.”

Tàbí “Pẹ̀tẹ́lẹ̀.”

Tàbí “olóòótọ́.” Ní Héb., “Àmín.”

Tàbí “olóòótọ́.” Ní Héb., “Àmín.”

Tàbí “ìṣòro.”

Tàbí kó jẹ́, “Ẹni ègún la sì máa ka ẹni tí kò bá lò tó ọgọ́rùn-ún ọdún sí.”

Tàbí “ṣe làálàá.”

Tàbí “ṣiṣẹ́ àṣedànù.”

Ní Héb., “èso.”

Tàbí “ṣàníyàn.”

Tàbí kó jẹ́, “ẹni tó ń ki òrìṣà.”

Tàbí “mú ọkàn wọn yọ̀.”

Tàbí “ṣàníyàn.”

Tàbí “agbára.”

Tàbí “gbogbo èèyàn.”

Ìyẹn, àwọn ọgbà tí wọ́n dìídì ṣe fún ìjọsìn òrìṣà.

Ní Héb., “èso.”

Tàbí “Gbogbo èèyàn.”

Tàbí “jọ́sìn.”

Ní Héb., “gbogbo ẹran ara.”

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́