NỌ́ŃBÀ
1 Jèhófà bá Mósè sọ̀rọ̀ ní aginjù Sínáì,+ nínú àgọ́ ìpàdé,+ ní ọjọ́ kìíní oṣù kejì, ọdún kejì tí wọ́n kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì.+ Ó sọ pé: 2 “Ẹ ka+ gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì* lọ́kọ̀ọ̀kan,* ní ìdílé-ìdílé, agbo ilé bàbá wọn, kí ẹ fi orúkọ ka gbogbo ọkùnrin. 3 Kí ìwọ àti Áárónì fi orúkọ gbogbo àwọn tó lè dara pọ̀ mọ́ àwọn ọmọ ogun Ísírẹ́lì sílẹ̀, ní àwùjọ-àwùjọ,* láti ẹni ogún (20) ọdún sókè.+
4 “Kí ẹ mú ọkùnrin kan látinú ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan; kí ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn jẹ́ olórí agbo ilé bàbá+ rẹ̀. 5 Orúkọ àwọn ọkùnrin tó máa dúró tì yín nìyí: ní ẹ̀yà Rúbẹ́nì, Élísúrì+ ọmọ Ṣédéúrì; 6 ní ẹ̀yà Síméónì, Ṣẹ́lúmíẹ́lì+ ọmọ Súríṣádáì; 7 ní ẹ̀yà Júdà, Náṣónì+ ọmọ Ámínádábù; 8 ní ẹ̀yà Ísákà, Nétánélì+ ọmọ Súárì; 9 ní ẹ̀yà Sébúlúnì, Élíábù+ ọmọ Hélónì; 10 nínú àwọn ọmọ Jósẹ́fù: látinú ẹ̀yà Éfúrémù,+ Élíṣámà ọmọ Ámíhúdù; látinú ẹ̀yà Mánásè, Gàmálíẹ́lì ọmọ Pédásúrì; 11 ní ẹ̀yà Bẹ́ńjámínì, Ábídánì+ ọmọ Gídéónì; 12 ní ẹ̀yà Dánì, Áhíésérì+ ọmọ Ámíṣádáì; 13 ní ẹ̀yà Áṣérì, Págíẹ́lì+ ọmọ Ókíránì; 14 ní ẹ̀yà Gádì, Élíásáfù+ ọmọ Déúélì; 15 ní ẹ̀yà Náfútálì, Áhírà+ ọmọ Énánì. 16 Àwọn yìí ni wọ́n pè látinú àpéjọ náà. Wọ́n jẹ́ ìjòyè+ nínú ẹ̀yà àwọn bàbá wọn, olórí ẹgbẹẹgbẹ̀rún ní Ísírẹ́lì.”+
17 Mósè àti Áárónì wá mú àwọn ọkùnrin tí wọ́n forúkọ pè yìí. 18 Wọ́n pe gbogbo àwọn èèyàn náà jọ ní ọjọ́ kìíní oṣù kejì, kí wọ́n lè forúkọ sílẹ̀ lọ́kọ̀ọ̀kan, ní ìdílé-ìdílé àti agbo ilé bàbá wọn, láti ẹni ogún (20) ọdún sókè,+ 19 bí Jèhófà ṣe pa á láṣẹ fún Mósè. Ó forúkọ wọn sílẹ̀ ní aginjù Sínáì.+
20 Wọ́n fi orúkọ wọn, ìdílé wọn àti agbo ilé bàbá wọn to àwọn ọmọkùnrin Rúbẹ́nì, àwọn àtọmọdọ́mọ àkọ́bí+ Ísírẹ́lì. Gbogbo ọkùnrin tó jẹ́ ẹni ogún (20) ọdún sókè, tó lè dara pọ̀ mọ́ àwọn ọmọ ogun ni wọ́n kà lọ́kọ̀ọ̀kan, 21 iye àwọn tí wọ́n sì forúkọ wọn sílẹ̀ nínú ẹ̀yà Rúbẹ́nì jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́rìndínláàádọ́ta ó lé ọgọ́rùn-ún márùn-ún (46,500).
22 Wọ́n fi orúkọ wọn, ìdílé wọn àti agbo ilé bàbá wọn to àwọn àtọmọdọ́mọ Síméónì.+ Gbogbo ọkùnrin tó jẹ́ ẹni ogún (20) ọdún sókè, tó lè dara pọ̀ mọ́ àwọn ọmọ ogun ni wọ́n kà lọ́kọ̀ọ̀kan, 23 iye àwọn tí wọ́n sì forúkọ wọn sílẹ̀ nínú ẹ̀yà Síméónì jẹ́ ẹgbẹ̀rún mọ́kàndínlọ́gọ́ta ó lé ọgọ́rùn-ún mẹ́ta (59,300).
24 Wọ́n fi orúkọ wọn, ìdílé wọn àti agbo ilé bàbá wọn to àwọn àtọmọdọ́mọ Gádì.+ Gbogbo ọkùnrin tó jẹ́ ẹni ogún (20) ọdún sókè, tó lè dara pọ̀ mọ́ àwọn ọmọ ogun ni wọ́n kà, 25 iye àwọn tí wọ́n sì forúkọ wọn sílẹ̀ nínú ẹ̀yà Gádì jẹ́ ẹgbẹ̀rún márùndínláàádọ́ta ó lé ọgọ́rùn-ún mẹ́fà àti àádọ́ta (45,650).
26 Wọ́n fi orúkọ wọn, ìdílé wọn àti agbo ilé bàbá wọn to àwọn àtọmọdọ́mọ Júdà.+ Gbogbo ọkùnrin tó jẹ́ ẹni ogún (20) ọdún sókè, tó lè dara pọ̀ mọ́ àwọn ọmọ ogun ni wọ́n kà, 27 iye àwọn tí wọ́n sì forúkọ wọn sílẹ̀ nínú ẹ̀yà Júdà jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́rìnléláàádọ́rin ó lé ọgọ́rùn-ún mẹ́fà (74,600).
28 Wọ́n fi orúkọ wọn, ìdílé wọn àti agbo ilé bàbá wọn to àwọn àtọmọdọ́mọ Ísákà.+ Gbogbo ọkùnrin tó jẹ́ ẹni ogún (20) ọdún sókè, tó lè dara pọ̀ mọ́ àwọn ọmọ ogun ni wọ́n kà, 29 iye àwọn tí wọ́n sì forúkọ wọn sílẹ̀ nínú ẹ̀yà Ísákà jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́rìnléláàádọ́ta ó lé ọgọ́rùn-ún mẹ́rin (54,400).
30 Wọ́n fi orúkọ wọn, ìdílé wọn àti agbo ilé bàbá wọn to àwọn àtọmọdọ́mọ Sébúlúnì.+ Gbogbo ọkùnrin tó jẹ́ ẹni ogún (20) ọdún sókè, tó lè dara pọ̀ mọ́ àwọn ọmọ ogun ni wọ́n kà, 31 iye àwọn tí wọ́n sì forúkọ wọn sílẹ̀ nínú ẹ̀yà Sébúlúnì jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́tàdínlọ́gọ́ta ó lé ọgọ́rùn-ún mẹ́rin (57,400).
32 Wọ́n fi orúkọ wọn, ìdílé wọn àti agbo ilé bàbá wọn to àwọn àtọmọdọ́mọ Jósẹ́fù nípasẹ̀ Éfúrémù.+ Gbogbo ọkùnrin tó jẹ́ ẹni ogún (20) ọdún sókè, tó lè dara pọ̀ mọ́ àwọn ọmọ ogun ni wọ́n kà, 33 iye àwọn tí wọ́n sì forúkọ wọn sílẹ̀ nínú ẹ̀yà Éfúrémù jẹ́ ẹgbẹ̀rún lọ́nà ogójì ó lé ọgọ́rùn-ún márùn-ún (40,500).
34 Wọ́n fi orúkọ wọn, ìdílé wọn àti agbo ilé bàbá wọn to àwọn àtọmọdọ́mọ Mánásè.+ Gbogbo ọkùnrin tó jẹ́ ẹni ogún (20) ọdún sókè, tó lè dara pọ̀ mọ́ àwọn ọmọ ogun ni wọ́n kà, 35 iye àwọn tí wọ́n sì forúkọ wọn sílẹ̀ nínú ẹ̀yà Mánásè jẹ́ ẹgbẹ̀rún lọ́nà méjìlélọ́gbọ̀n ó lé igba (32,200).
36 Wọ́n fi orúkọ wọn, ìdílé wọn àti agbo ilé bàbá wọn to àwọn àtọmọdọ́mọ Bẹ́ńjámínì.+ Gbogbo ọkùnrin tó jẹ́ ẹni ogún (20) ọdún sókè, tó lè dara pọ̀ mọ́ àwọn ọmọ ogun ni wọ́n kà, 37 iye àwọn tí wọ́n sì forúkọ wọn sílẹ̀ nínú ẹ̀yà Bẹ́ńjámínì jẹ́ ẹgbẹ̀rún márùndínlógójì ó lé ọgọ́rùn-ún mẹ́rin (35,400).
38 Wọ́n fi orúkọ wọn, ìdílé wọn àti agbo ilé bàbá wọn to àwọn àtọmọdọ́mọ Dánì.+ Gbogbo ọkùnrin tó jẹ́ ẹni ogún (20) ọdún sókè, tó lè dara pọ̀ mọ́ àwọn ọmọ ogun ni wọ́n kà, 39 iye àwọn tí wọ́n sì forúkọ wọn sílẹ̀ nínú ẹ̀yà Dánì jẹ́ ẹgbẹ̀rún méjìlélọ́gọ́ta ó lé ọgọ́rùn-ún méje (62,700).
40 Wọ́n fi orúkọ wọn, ìdílé wọn àti agbo ilé bàbá wọn to àwọn àtọmọdọ́mọ Áṣérì.+ Gbogbo ọkùnrin tó jẹ́ ẹni ogún (20) ọdún sókè, tó lè dara pọ̀ mọ́ àwọn ọmọ ogun ni wọ́n kà, 41 iye àwọn tí wọ́n sì forúkọ wọn sílẹ̀ nínú ẹ̀yà Áṣérì jẹ́ ẹgbẹ̀rún mọ́kànlélógójì ó lé ọgọ́rùn-ún márùn-ún (41,500).
42 Wọ́n fi orúkọ wọn, ìdílé wọn àti agbo ilé bàbá wọn to àwọn àtọmọdọ́mọ Náfútálì.+ Gbogbo ọkùnrin tó jẹ́ ẹni ogún (20) ọdún sókè, tó lè dara pọ̀ mọ́ àwọn ọmọ ogun ni wọ́n kà, 43 iye àwọn tí wọ́n sì forúkọ wọn sílẹ̀ nínú ẹ̀yà Náfútálì jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́tàléláàádọ́ta ó lé ọgọ́rùn-ún mẹ́rin (53,400).
44 Èyí ni àwọn tí Mósè pẹ̀lú Áárónì àti àwọn ìjòyè méjìlá (12) Ísírẹ́lì forúkọ wọn sílẹ̀, ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn ṣojú fún agbo ilé bàbá rẹ̀. 45 Gbogbo ọmọ Ísírẹ́lì tó jẹ́ ẹni ogún (20) ọdún sókè tó lè dara pọ̀ mọ́ àwọn ọmọ ogun Ísírẹ́lì ni wọ́n forúkọ wọn sílẹ̀ bí wọ́n ṣe wà nínú agbo ilé bàbá wọn, 46 gbogbo àwọn tí wọ́n forúkọ wọn sílẹ̀ sì jẹ́ ọgbọ̀n ọ̀kẹ́ ó lé ẹgbẹ̀rún mẹ́ta ààbọ̀ àti àádọ́ta (603,550).+
47 Àmọ́ wọn ò forúkọ àwọn ọmọ Léfì+ sílẹ̀ pẹ̀lú àwọn yòókù bí wọ́n ṣe wà nínú ẹ̀yà bàbá+ wọn. 48 Jèhófà wá sọ fún Mósè pé: 49 “Ẹ̀yà Léfì nìkan ni ìwọ kò gbọ́dọ̀ forúkọ wọn sílẹ̀, má sì kà wọ́n mọ́ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì+ yòókù. 50 Kí o yan àwọn ọmọ Léfì láti máa bójú tó àgọ́ Ẹ̀rí+ àti gbogbo ohun èlò rẹ̀ pẹ̀lú gbogbo ohun tó jẹ́ ti àgọ́ náà.+ Kí wọ́n máa gbé àgọ́ ìjọsìn náà àti gbogbo ohun èlò rẹ̀,+ kí wọ́n máa ṣiṣẹ́ níbẹ̀,+ kí wọ́n sì pàgọ́ yí àgọ́ ìjọsìn+ náà ká. 51 Nígbàkigbà tí ẹ bá fẹ́ kó àgọ́ ìjọsìn náà kúrò,+ àwọn ọmọ Léfì ni kó tú u palẹ̀; tí ẹ bá sì fẹ́ to àgọ́ ìjọsìn náà pa dà, àwọn ọmọ Léfì ni kó tò ó; tí ẹnikẹ́ni tí kò lẹ́tọ̀ọ́* bá sún mọ́ ọn, ṣe ni kí ẹ pa á.+
52 “Kí ọmọ Ísírẹ́lì kọ̀ọ̀kan pa àgọ́ rẹ̀ sí ibi tí wọ́n yàn fún un, ọkùnrin kọ̀ọ̀kan níbi tí wọ́n pín àwọn ẹ̀yà sí ní mẹ́ta-mẹ́ta,*+ ní àwùjọ-àwùjọ.* 53 Kí àwọn ọmọ Léfì sì pàgọ́ yí àgọ́ Ẹ̀rí ká, kí n má bàa bínú sí àpéjọ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì;+ àwọn ọmọ Léfì ni kó máa bójú tó* àgọ́ ìjọsìn Ẹ̀rí+ náà.”
54 Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe gbogbo ohun tí Jèhófà pa láṣẹ fún Mósè. Wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀ gẹ́lẹ́.
2 Jèhófà wá sọ fún Mósè àti Áárónì pé: 2 “Kí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pàgọ́ síbi tí wọ́n pín àwọn ẹ̀yà wọn sí ní mẹ́ta-mẹ́ta,+ kí ọkùnrin kọ̀ọ̀kan pàgọ́ síbi àkọlé* agbo ilé bàbá rẹ̀. Kí àgọ́ wọn dojú kọ àgọ́ ìpàdé, kí wọ́n pàgọ́ yí i ká.
3 “Kí ẹ̀yà mẹ́ta ti ibùdó Júdà pàgọ́ sí ìlà oòrùn, lápá ibi tí oòrùn ti ń yọ, ní àwùjọ-àwùjọ;* Náṣónì+ ọmọ Ámínádábù ni ìjòyè àwọn ọmọ Júdà. 4 Àwọn tí wọ́n forúkọ wọn sílẹ̀ nínú àwọn ọmọ ogun rẹ̀ jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́rìnléláàádọ́rin ó lé ọgọ́rùn-ún mẹ́fà (74,600).+ 5 Kí ẹ̀yà Ísákà pàgọ́ sí ẹ̀gbẹ́ wọn; Nétánélì+ ọmọ Súárì ni ìjòyè àwọn ọmọ Ísákà. 6 Àwọn tí wọ́n forúkọ wọn sílẹ̀ nínú àwọn ọmọ ogun rẹ̀ jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́rìnléláàádọ́ta ó lé ọgọ́rùn-ún mẹ́rin (54,400).+ 7 Kí ẹ̀yà Sébúlúnì wá tẹ̀ lé wọn; Élíábù+ ọmọ Hélónì ni ìjòyè àwọn ọmọ Sébúlúnì. 8 Àwọn tí wọ́n forúkọ wọn sílẹ̀ nínú àwọn ọmọ ogun rẹ̀ jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́tàdínlọ́gọ́ta ó lé ọgọ́rùn-ún mẹ́rin (57,400).+
9 “Gbogbo àwọn tí wọ́n forúkọ wọn sílẹ̀ nínú àwọn ọmọ ogun ibùdó Júdà jẹ́ ọ̀kẹ́ mẹ́sàn-án ó lé ẹgbẹ̀rún mẹ́fà àti ọgọ́rùn-ún mẹ́rin (186,400). Àwọn ni kó kọ́kọ́ máa tú àgọ́ wọn ká.+
10 “Kí ẹ̀yà mẹ́ta ti ibùdó Rúbẹ́nì+ wà ní apá gúúsù, ní àwùjọ-àwùjọ;* Élísúrì+ ọmọ Ṣédéúrì ni ìjòyè àwọn ọmọ Rúbẹ́nì. 11 Àwọn tí wọ́n forúkọ wọn sílẹ̀ nínú àwọn ọmọ ogun rẹ̀ jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́rìndínláàádọ́ta ó lé ọgọ́rùn-ún márùn-ún (46,500).+ 12 Kí ẹ̀yà Síméónì pàgọ́ sí ẹ̀gbẹ́ wọn; Ṣẹ́lúmíẹ́lì+ ọmọ Súríṣádáì ni ìjòyè àwọn ọmọ Síméónì. 13 Àwọn tí wọ́n forúkọ wọn sílẹ̀ nínú àwọn ọmọ ogun rẹ̀ jẹ́ ẹgbẹ̀rún mọ́kàndínlọ́gọ́ta ó lé ọgọ́rùn-ún mẹ́ta (59,300).+ 14 Kí ẹ̀yà Gádì wá tẹ̀ lé wọn; Élíásáfù+ ọmọ Rúẹ́lì ni ìjòyè àwọn ọmọ Gádì. 15 Àwọn tí wọ́n forúkọ wọn sílẹ̀ nínú àwọn ọmọ ogun rẹ̀ jẹ́ ẹgbẹ̀rún márùndínláàádọ́ta ó lé ọgọ́rùn-ún mẹ́fà àti àádọ́ta (45,650).+
16 “Gbogbo àwọn tí wọ́n forúkọ wọn sílẹ̀ nínú àwọn ọmọ ogun ibùdó Rúbẹ́nì jẹ́ ẹgbẹ̀rún mọ́kànléláàádọ́jọ ó lé ọgọ́rùn-ún mẹ́rin àti àádọ́ta (151,450), àwọn ni kó sì máa tú àgọ́ wọn ká ṣìkejì.+
17 “Nígbà tí ẹ bá ń gbé àgọ́ ìpàdé kúrò,+ àgọ́ àwọn ọmọ Léfì ni kó wà láàárín àwọn àgọ́ yòókù.
“Bí wọ́n bá ṣe pàgọ́ náà ni kí wọ́n ṣe tẹ̀ léra tí wọ́n bá ń rìnrìn àjò,+ kí kálukú wà ní àyè rẹ̀, bí wọ́n ṣe pín ẹ̀yà wọn ní mẹ́ta-mẹ́ta.
18 “Kí ẹ̀yà mẹ́ta ti ibùdó Éfúrémù wà ní apá ìwọ̀ oòrùn, ní àwùjọ-àwùjọ;* Élíṣámà+ ọmọ Ámíhúdù ni ìjòyè àwọn ọmọ Éfúrémù. 19 Àwọn tí wọ́n forúkọ wọn sílẹ̀ nínú àwọn ọmọ ogun rẹ̀ jẹ́ ẹgbẹ̀rún lọ́nà ogójì ó lé ọgọ́rùn-ún márùn-ún (40,500).+ 20 Kí ẹ̀yà Mánásè+ pàgọ́ sí ẹ̀gbẹ́ wọn; Gàmálíẹ́lì+ ọmọ Pédásúrì ni ìjòyè àwọn ọmọ Mánásè. 21 Àwọn tí wọ́n forúkọ wọn sílẹ̀ nínú àwọn ọmọ ogun rẹ̀ jẹ́ ẹgbẹ̀rún méjìlélọ́gbọ̀n ó lé igba (32,200).+ 22 Kí ẹ̀yà Bẹ́ńjámínì wá tẹ̀ lé wọn; Ábídánì+ ọmọ Gídéónì ni ìjòyè àwọn ọmọ Bẹ́ńjámínì. 23 Àwọn tí wọ́n forúkọ wọn sílẹ̀ nínú àwọn ọmọ ogun rẹ̀ jẹ́ ẹgbẹ̀rún márùndínlógójì ó lé ọgọ́rùn-ún mẹ́rin (35,400).+
24 “Gbogbo àwọn tí wọ́n forúkọ wọn sílẹ̀ nínú àwọn ọmọ ogun ibùdó Éfúrémù jẹ́ ẹgbẹ̀rún méjìdínláàádọ́fà ó lé ọgọ́rùn-ún (108,100), àwọn ni kó sì máa tú àgọ́ wọn ká ṣìkẹta.+
25 “Kí ẹ̀yà mẹ́ta ti ibùdó Dánì wà ní apá àríwá, ní àwùjọ-àwùjọ;* Áhíésérì+ ọmọ Ámíṣádáì ni ìjòyè àwọn ọmọ Dánì. 26 Àwọn tí wọ́n forúkọ wọn sílẹ̀ nínú àwọn ọmọ ogun rẹ̀ jẹ́ ẹgbẹ̀rún méjìlélọ́gọ́ta ó lé ọgọ́rùn-ún méje (62,700).+ 27 Kí ẹ̀yà Áṣérì pàgọ́ sí ẹ̀gbẹ́ wọn; Págíẹ́lì+ ọmọ Ókíránì ni ìjòyè àwọn ọmọ Áṣérì. 28 Àwọn tí wọ́n forúkọ wọn sílẹ̀ nínú àwọn ọmọ ogun rẹ̀ jẹ́ ẹgbẹ̀rún mọ́kànlélógójì ó lé ọgọ́rùn-ún márùn-ún (41,500).+ 29 Kí ẹ̀yà Náfútálì wá tẹ̀ lé wọn; Áhírà+ ọmọ Énánì ni ìjòyè àwọn ọmọ Náfútálì. 30 Àwọn tí wọ́n forúkọ wọn sílẹ̀ nínú àwọn ọmọ ogun rẹ̀ jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́tàléláàádọ́ta ó lé ọgọ́rùn-ún mẹ́rin (53,400).+
31 “Gbogbo àwọn tí wọ́n forúkọ wọn sílẹ̀ nínú ibùdó Dánì jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́tàdínlọ́gọ́jọ ó lé ọgọ́rùn-ún mẹ́fà (157,600). Àwọn ni kó máa tú àgọ́ wọn ká kẹ́yìn,+ bí wọ́n ṣe pín ẹ̀yà wọn ní mẹ́ta-mẹ́ta.”
32 Èyí ni àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tí wọ́n forúkọ wọn sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí agbo ilé bàbá wọn; gbogbo àwọn tó wà nínú àwọn ibùdó tí wọ́n forúkọ wọn sílẹ̀ láti dara pọ̀ mọ́ àwọn ọmọ ogun jẹ́ ọgbọ̀n ọ̀kẹ́ ó lé ẹgbẹ̀rún mẹ́ta ààbọ̀ àti àádọ́ta (603,550).+ 33 Àmọ́ wọn ò forúkọ àwọn ọmọ Léfì sílẹ̀+ pẹ̀lú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì+ yòókù, bí Jèhófà ṣe pa á láṣẹ fún Mósè. 34 Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe gbogbo ohun tí Jèhófà pa láṣẹ fún Mósè. Báyìí ni wọ́n ṣe ń pàgọ́, lọ́nà mẹ́ta-mẹ́ta tí wọ́n pín ẹ̀yà wọn sí,+ tí wọ́n sì máa ń tú àgọ́ wọn ká,+ ní ìdílé-ìdílé àti agbo ilé bàbá wọn.
3 Èyí ni àwọn ìlà ìdílé* Áárónì àti Mósè ní ọjọ́ tí Jèhófà bá Mósè sọ̀rọ̀ lórí Òkè Sínáì.+ 2 Orúkọ àwọn ọmọkùnrin Áárónì nìyí: Nádábù àkọ́bí, Ábíhù,+ Élíásárì+ àti Ítámárì.+ 3 Èyí ní àwọn ọmọkùnrin Áárónì, àwọn àlùfáà tí wọ́n fòróró yàn, tí wọ́n fi iṣẹ́ àlùfáà+ lé lọ́wọ́.* 4 Àmọ́ Nádábù àti Ábíhù kú níwájú Jèhófà nígbà tí wọ́n rú ẹbọ tí kò tọ́ níwájú Jèhófà+ ní aginjù Sínáì, wọn ò sì bímọ kankan. Àmọ́ Élíásárì+ àti Ítámárì+ ṣì ń ṣiṣẹ́ àlùfáà pẹ̀lú Áárónì bàbá wọn.
5 Jèhófà wá sọ fún Mósè pé: 6 “Jẹ́ kí ẹ̀yà Léfì+ wá síwájú, kí o sì ní kí wọ́n dúró níwájú àlùfáà Áárónì, kí wọ́n máa ṣe ìránṣẹ́+ fún un. 7 Kí wọ́n máa ṣe iṣẹ́ wọn ní àgọ́ ìjọsìn, èyí ni ojúṣe wọn fún un àti fún gbogbo àpéjọ náà níwájú àgọ́ ìpàdé. 8 Kí wọ́n máa bójú tó gbogbo ohun èlò+ àgọ́ ìpàdé, kí wọ́n sì máa ṣe iṣẹ́ tó jẹ mọ́ àgọ́ ìjọsìn,+ èyí ni ojúṣe wọn fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì. 9 Kí o fún Áárónì àti àwọn ọmọ rẹ̀ ní àwọn ọmọ Léfì. Àwọn ni a fi fúnni, a fún un látinú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.+ 10 Kí o yan Áárónì àti àwọn ọmọ rẹ̀, kí wọ́n máa ṣe iṣẹ́ àlùfáà,+ tí ẹnikẹ́ni tí kò lẹ́tọ̀ọ́* sí i bá sì sún mọ́ tòsí, ṣe ni kí ẹ pa á.”+
11 Jèhófà ń bá ọ̀rọ̀ tó ń sọ fún Mósè lọ pé: 12 “Wò ó! Ní tèmi, mo mú àwọn ọmọ Léfì látinú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì dípò gbogbo àkọ́bí* àwọn ọmọ Ísírẹ́lì,+ àwọn ọmọ Léfì yóò sì di tèmi. 13 Torí tèmi+ ni gbogbo àkọ́bí. Lọ́jọ́ tí mo pa gbogbo àkọ́bí nílẹ̀ Íjíbítì,+ mo ya gbogbo àkọ́bí ní Ísírẹ́lì sí mímọ́ fún ara mi, látorí èèyàn dórí ẹranko.+ Wọ́n á di tèmi. Èmi ni Jèhófà.”
14 Jèhófà tún sọ fún Mósè ní aginjù Sínáì+ pé: 15 “Fi orúkọ àwọn ọmọkùnrin Léfì sílẹ̀ bí wọ́n ṣe wà nínú agbo ilé bàbá wọn àti ìdílé wọn. Gbogbo ọkùnrin tó jẹ́ ọmọ oṣù kan sókè+ ni kí o forúkọ wọn sílẹ̀.” 16 Torí náà, Mósè fi orúkọ wọn sílẹ̀ bí Jèhófà ṣe sọ, tó sì pa á láṣẹ fún un. 17 Orúkọ àwọn ọmọkùnrin Léfì nìyí: Gẹ́ṣónì, Kóhátì àti Mérárì.+
18 Orúkọ àwọn ọmọ Gẹ́ṣónì nìyí ní ìdílé-ìdílé: Líbínì àti Ṣíméì.+
19 Àwọn ọmọ Kóhátì gẹ́gẹ́ bí ìdílé wọn ni Ámúrámù, Ísárì, Hébúrónì àti Úsíélì.+
20 Àwọn ọmọ Mérárì gẹ́gẹ́ bí ìdílé wọn ni Máhílì+ àti Múṣì.+
Ìdílé àwọn ọmọ Léfì nìyí, gẹ́gẹ́ bí agbo ilé bàbá wọn.
21 Ọ̀dọ̀ Gẹ́ṣónì ni ìdílé àwọn ọmọ Líbínì+ àti ìdílé àwọn ọmọ Ṣíméì ti ṣẹ̀ wá. Ìwọ̀nyí ni ìdílé àwọn ọmọ Gẹ́ṣónì. 22 Gbogbo ọkùnrin tó jẹ́ ọmọ oṣù kan sókè tí wọ́n forúkọ wọn sílẹ̀ jẹ́ ẹgbẹ̀rún méje ààbọ̀ (7,500).+ 23 Ẹ̀yìn àgọ́ ìjọsìn+ lápá ìwọ̀ oòrùn ni ìdílé àwọn ọmọ Gẹ́ṣónì pàgọ́ sí. 24 Élíásáfù ọmọ Láélì ni ìjòyè agbo ilé bàbá àwọn ọmọ Gẹ́ṣónì. 25 Ojúṣe àwọn ọmọ Gẹ́ṣónì+ nínú àgọ́ ìpàdé ni pé kí wọ́n máa bójú tó àgọ́ ìjọsìn àti àgọ́,*+ ìbòrí rẹ̀,+ aṣọ* tí wọ́n ta+ sí ẹnu ọ̀nà àgọ́ ìpàdé, 26 àwọn aṣọ ìdábùú+ tí wọ́n ta sí àgbàlá, aṣọ* tí wọ́n ta+ sí ẹnu ọ̀nà àgbàlá tó yí àgọ́ ìjọsìn àti pẹpẹ ká, àwọn okùn àgọ́ rẹ̀ àti gbogbo iṣẹ́ tó jẹ mọ́ nǹkan wọ̀nyí.
27 Ọ̀dọ̀ Kóhátì ni ìdílé àwọn ọmọ Ámúrámù ti ṣẹ̀ wá, pẹ̀lú ìdílé àwọn ọmọ Ísárì, ìdílé àwọn ọmọ Hébúrónì àti ìdílé àwọn ọmọ Úsíélì. Ìwọ̀nyí ni ìdílé àwọn ọmọ Kóhátì.+ 28 Gbogbo ọkùnrin tó jẹ́ ọmọ oṣù kan sókè jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́jọ ó lé ọgọ́rùn-ún mẹ́fà (8,600); ojúṣe wọn ni pé kí wọ́n máa bójú tó ibi mímọ́.+ 29 Apá gúúsù àgọ́ ìjọsìn+ ni ìdílé àwọn ọmọ Kóhátì pàgọ́ sí. 30 Élísáfánì ọmọ Úsíélì+ ni ìjòyè agbo ilé ní ìdílé àwọn ọmọ Kóhátì. 31 Ojúṣe wọn ni pé kí wọ́n máa bójú tó Àpótí,+ tábìlì,+ ọ̀pá fìtílà,+ àwọn pẹpẹ,+ àwọn ohun èlò+ tí wọ́n fi ń ṣiṣẹ́ ní ibi mímọ́, aṣọ* tí wọ́n ta+ sí ẹnu ọ̀nà àti gbogbo iṣẹ́ tó jẹ mọ́ nǹkan wọ̀nyí.+
32 Olórí ìjòyè àwọn ọmọ Léfì ni Élíásárì+ ọmọ àlùfáà Áárónì, òun ló ń darí àwọn tó ń bójú tó iṣẹ́ ní ibi mímọ́.
33 Látọ̀dọ̀ Mérárì ni ìdílé àwọn ọmọ Máhílì àti ìdílé àwọn ọmọ Múṣì ti ṣẹ̀ wá. Ìwọ̀nyí ni àwọn ìdílé Mérárì.+ 34 Gbogbo ọkùnrin tó jẹ́ ọmọ oṣù kan sókè tí wọ́n forúkọ wọn sílẹ̀ jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́fà ó lé igba (6,200).+ 35 Súríélì ọmọ Ábíháílì ni ìjòyè agbo ilé nínú àwọn ìdílé Mérárì. Apá àríwá àgọ́ ìjọsìn+ ni wọ́n pàgọ́ sí. 36 Ojúṣe àwọn ọmọ Mérárì ni pé kí wọ́n máa bójú tó àwọn férémù+ àgọ́ ìjọsìn, àwọn ọ̀pá gbọọrọ rẹ̀,+ àwọn òpó rẹ̀,+ àwọn ìtẹ́lẹ̀ oníhò rẹ̀, gbogbo ohun èlò+ rẹ̀ àti gbogbo iṣẹ́ tó jẹ mọ́ nǹkan wọ̀nyí,+ 37 títí kan àwọn òpó tó yí àgbàlá náà ká àti àwọn ìtẹ́lẹ̀ oníhò+ wọn, èèkàn àgọ́ wọn àti okùn àgọ́ wọn.
38 Mósè àti Áárónì àti àwọn ọmọ rẹ̀ ló pàgọ́ síwájú àgọ́ ìjọsìn lápá ìlà oòrùn, níwájú àgọ́ ìpàdé lápá ibi tí oòrùn ti ń yọ. Ojúṣe wọn sí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ni pé kí wọ́n máa bójú tó ibi mímọ́. Tí ẹnikẹ́ni tí kò lẹ́tọ̀ọ́ sí i* bá sún mọ́ tòsí, ṣe ni wọ́n máa pa á.+
39 Gbogbo ọmọ Léfì tó jẹ́ ọkùnrin láti ọmọ oṣù kan sókè, tí Mósè àti Áárónì forúkọ wọn sílẹ̀ ní ìdílé-ìdílé, bí Jèhófà ṣe pa á láṣẹ jẹ́ ẹgbẹ̀rún méjìlélógún (22,000).
40 Jèhófà wá sọ fún Mósè pé: “Fi orúkọ gbogbo àkọ́bí tó jẹ́ ọkùnrin nínú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sílẹ̀, láti ọmọ oṣù kan sókè,+ kà wọ́n, kí o sì kọ orúkọ wọn. 41 Èmi ni Jèhófà, kí o mú àwọn ọmọ Léfì fún mi dípò gbogbo àkọ́bí nínú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì,+ kí o sì mú ẹran ọ̀sìn àwọn ọmọ Léfì dípò gbogbo àkọ́bí ẹran ọ̀sìn àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.”+ 42 Mósè wá forúkọ gbogbo àkọ́bí nínú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sílẹ̀, bí Jèhófà ṣe pa á láṣẹ fún un. 43 Gbogbo àkọ́bí tó jẹ́ ọkùnrin tí wọ́n forúkọ wọn sílẹ̀ láti ẹni oṣù kan sókè jẹ́ ẹgbẹ̀rún méjìlélógún ó lé igba àti mẹ́tàléláàádọ́rin (22,273).
44 Jèhófà ń bá ọ̀rọ̀ tó ń sọ fún Mósè lọ pé: 45 “Mú àwọn ọmọ Léfì dípò gbogbo àkọ́bí nínú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, kí o sì mú ẹran ọ̀sìn àwọn ọmọ Léfì dípò àwọn ẹran ọ̀sìn wọn, àwọn ọmọ Léfì yóò sì di tèmi. Èmi ni Jèhófà. 46 Láti san owó ìràpadà+ fún igba ó lé mẹ́tàléláàádọ́rin (273) àkọ́bí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, iye tí wọ́n fi pọ̀ ju àwọn ọmọ Léfì+ lọ, 47 kí o gba ṣékélì* márùn-ún lọ́wọ́ ẹnì kọ̀ọ̀kan,+ kó jẹ́ ìwọ̀n ṣékélì ibi mímọ́.* Ṣékélì kan jẹ́ ogún (20) òṣùwọ̀n gérà.*+ 48 Kí o kó owó náà fún Áárónì àti àwọn ọmọ rẹ̀, ó jẹ́ owó ìràpadà àwọn tó ṣẹ́ kù lára wọn.” 49 Mósè wá gba owó ìràpadà náà lọ́wọ́ àwọn tó ṣẹ́ kù lẹ́yìn tí àwọn ọmọ Léfì ṣe ìràpadà. 50 Ó gba owó náà lọ́wọ́ àwọn àkọ́bí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, iye rẹ̀ jẹ́ ẹgbẹ̀rún kan ó lé ọgọ́rùn-ún mẹ́ta àti márùndínláàádọ́rin (1,365) ṣékélì, ó jẹ́ ṣékélì ibi mímọ́. 51 Mósè wá kó owó ìràpadà náà fún Áárónì àti àwọn ọmọ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀* Jèhófà, bí Jèhófà ṣe pa á láṣẹ fún Mósè.
4 Lẹ́yìn náà, Jèhófà sọ fún Mósè àti Áárónì pé: 2 “Ẹ ka àwọn ọmọ Kóhátì+ lára àwọn ọmọ Léfì, ní ìdílé-ìdílé àti agbo ilé bàbá wọn, 3 gbogbo àwọn tó jẹ́ ẹni ọgbọ̀n (30)+ ọdún sí àádọ́ta (50) ọdún,+ tí wọ́n wà lára àwọn tí a yàn pé kí wọ́n máa ṣiṣẹ́ nínú àgọ́ ìpàdé.+
4 “Èyí ni iṣẹ́ àwọn ọmọ Kóhátì nínú àgọ́ ìpàdé.+ Ohun mímọ́ jù lọ ni: 5 Tí àwọn èèyàn* náà bá fẹ́ gbéra, kí Áárónì àti àwọn ọmọ rẹ̀ wọlé, kí wọ́n tú aṣọ ìdábùú+ kúrò, kí wọ́n sì fi bo àpótí+ Ẹ̀rí. 6 Kí wọ́n fi awọ séálì bò ó, kí wọ́n na aṣọ tó jẹ́ kìkì àwọ̀ búlúù sórí rẹ̀, kí wọ́n sì ki àwọn ọ̀pá tí wọ́n á fi gbé e+ bọ̀ ọ́.
7 “Kí wọ́n tún na aṣọ aláwọ̀ búlúù bo tábìlì búrẹ́dì àfihàn,+ kí wọ́n sì kó àwọn àwo ìjẹun sórí rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ife, àwọn abọ́ àti àwọn ṣágo ọrẹ ohun mímu;+ kí búrẹ́dì+ ọrẹ máa wà lórí rẹ̀ nígbà gbogbo. 8 Kí wọ́n na aṣọ aláwọ̀ rírẹ̀dòdò sórí wọn, kí wọ́n fi awọ séálì bò ó, kí wọ́n sì ki àwọn ọ̀pá tí wọ́n á fi gbé e+ bọ̀ ọ́. 9 Kí wọ́n wá mú aṣọ aláwọ̀ búlúù, kí wọ́n sì fi bo ọ̀pá fìtílà+ tí wọ́n fi ń tan iná,+ pẹ̀lú àwọn fìtílà rẹ̀, àwọn ìpaná* rẹ̀, àwọn ìkóná rẹ̀+ àti gbogbo ohun èlò rẹ̀ tí wọ́n ń fi òróró sí láti máa fi tàn án. 10 Kí wọ́n fi awọ séálì wé e pẹ̀lú gbogbo ohun èlò rẹ̀, kí wọ́n sì gbé e sórí ọ̀pá gbọọrọ tí wọ́n á fi gbé e. 11 Kí wọ́n na aṣọ aláwọ̀ búlúù sórí pẹpẹ wúrà,+ kí wọ́n fi awọ séálì bò ó, kí wọ́n sì ki àwọn ọ̀pá tí wọ́n á fi gbé e + bọ̀ ọ́. 12 Kí wọ́n wá kó gbogbo ohun èlò+ tí wọ́n fi ń ṣiṣẹ́, èyí tí wọ́n máa ń lò déédéé nínú ibi mímọ́, kí wọ́n kó o sínú aṣọ aláwọ̀ búlúù, kí wọ́n fi awọ séálì bò ó, kí wọ́n sì gbé e sórí ọ̀pá gbọọrọ tí wọ́n á fi gbé e.
13 “Kí wọ́n kó eérú* kúrò nínú pẹpẹ,+ kí wọ́n sì na aṣọ tí wọ́n fi òwú aláwọ̀ pọ́pù ṣe sórí rẹ̀. 14 Kí wọ́n kó gbogbo ohun èlò tí wọ́n fi ń ṣiṣẹ́ níbi pẹpẹ náà sórí rẹ̀: àwọn ìkóná, àwọn àmúga, àwọn ṣọ́bìrì àti àwọn abọ́, gbogbo ohun èlò pẹpẹ;+ kí wọ́n fi awọ séálì bò ó, kí wọ́n sì ki àwọn ọ̀pá+ tí wọ́n á fi gbé e bọ̀ ọ́.
15 “Áárónì àti àwọn ọmọ rẹ̀ gbọ́dọ̀ ti bo ibi mímọ́+ náà tán àti gbogbo ohun èlò ibi mímọ́ náà nígbà tí àwọn èèyàn* náà bá fẹ́ gbéra. Kí àwọn ọmọ Kóhátì wá wọlé wá gbé e,+ àmọ́ wọn ò gbọ́dọ̀ fara kan ibi mímọ́ kí wọ́n má bàa kú.+ Ojúṣe* àwọn ọmọ Kóhátì nínú àgọ́ ìpàdé nìyí.
16 “Élíásárì+ ọmọ àlùfáà Áárónì ló ń bójú tó òróró tí wọ́n fi ń tan iná,+ tùràrí onílọ́fínńdà,+ ọrẹ ọkà ìgbà gbogbo àti òróró àfiyanni.+ Òun ló ń bójú tó gbogbo àgọ́ ìjọsìn àti gbogbo ohun tó wà nínú rẹ̀, títí kan ibi mímọ́ àti àwọn ohun èlò rẹ̀.”
17 Jèhófà ń bá ọ̀rọ̀ tó ń sọ fún Mósè àti Áárónì lọ pé: 18 “Ẹ má ṣe jẹ́ kí ẹ̀yà ìdílé àwọn ọmọ Kóhátì+ pa run láàárín àwọn ọmọ Léfì. 19 Ohun tí ẹ máa ṣe fún wọn nìyí kí wọ́n lè máa wà láàyè, kí wọ́n má sì kú torí pé wọ́n sún mọ́ àwọn ohun mímọ́ jù lọ.+ Kí Áárónì àti àwọn ọmọ rẹ̀ wọlé, kí wọ́n yan iṣẹ́ kálukú àti ohun tó máa gbé fún un. 20 Wọn ò gbọ́dọ̀ wọlé wá wo àwọn ohun mímọ́, ì báà jẹ́ fírí, àìjẹ́ bẹ́ẹ̀, wọ́n máa kú.”+
21 Jèhófà wá sọ fún Mósè pé: 22 “Ka àwọn ọmọ Gẹ́ṣónì,+ gẹ́gẹ́ bí agbo ilé bàbá wọn àti ní ìdílé-ìdílé. 23 Kí o forúkọ wọn sílẹ̀, gbogbo àwọn tó jẹ́ ẹni ọgbọ̀n (30) ọdún sí àádọ́ta (50) ọdún, tí wọ́n wà lára àwọn tí a yàn pé kí wọ́n máa ṣiṣẹ́ nínú àgọ́ ìpàdé. 24 Iṣẹ́ tí ìdílé àwọn ọmọ Gẹ́ṣónì á máa ṣe àtàwọn ohun tí wọ́n á máa gbé+ nìyí: 25 Kí wọ́n máa gbé aṣọ àgọ́+ ti àgọ́ ìjọsìn, àgọ́ ìpàdé, ìbòrí rẹ̀ àti ìbòrí tí wọ́n fi awọ séálì ṣe tó wà lókè rẹ̀,+ aṣọ* tí wọ́n ta sí ẹnu ọ̀nà àgọ́ ìpàdé,+ 26 àwọn aṣọ ìdábùú tí wọ́n ta sí àgbàlá,+ aṣọ* tí wọ́n ta sí ẹnu ọ̀nà àgbàlá+ tó yí àgọ́ ìjọsìn àti pẹpẹ ká, àwọn okùn àgọ́ wọn àti gbogbo ohun èlò wọn pẹ̀lú gbogbo ohun tí wọ́n fi ń ṣiṣẹ́ níbẹ̀. Iṣẹ́ tí wọ́n á máa ṣe nìyí. 27 Kí Áárónì àti àwọn ọmọ rẹ̀ máa bójú tó gbogbo iṣẹ́ àti ẹrù àwọn ọmọ Gẹ́ṣónì;+ kí ẹ yan gbogbo ẹrù yìí fún wọn pé kó jẹ́ ojúṣe wọn. 28 Èyí ni iṣẹ́ tí ìdílé àwọn ọmọ Gẹ́ṣónì á máa ṣe nínú àgọ́ ìpàdé,+ Ítámárì+ ọmọ àlùfáà Áárónì ni yóò sì máa darí iṣẹ́ wọn.
29 “Ní ti àwọn ọmọ Mérárì,+ kí o forúkọ wọn sílẹ̀ ní ìdílé-ìdílé àti agbo ilé bàbá wọn. 30 Kí o forúkọ wọn sílẹ̀ láti ẹni ọgbọ̀n (30) ọdún sí àádọ́ta (50) ọdún, gbogbo ẹni tó wà lára àwọn tí a yàn pé kí wọ́n máa ṣiṣẹ́ nínú àgọ́ ìpàdé. 31 Àwọn ohun tí wọ́n á máa gbé+ tó jẹ mọ́ iṣẹ́ wọn nínú àgọ́ ìpàdé nìyí: àwọn férémù+ àgọ́ ìjọsìn, àwọn ọ̀pá ìdábùú+ rẹ̀, àwọn òpó+ rẹ̀, àwọn ìtẹ́lẹ̀ oníhò + rẹ̀; 32 àwọn òpó+ àgbàlá tó yí i ká, àwọn ìtẹ́lẹ̀ oníhò + wọn, àwọn èèkàn+ àgọ́ wọn àti àwọn okùn àgọ́ wọn pẹ̀lú gbogbo ohun èlò wọn àti gbogbo iṣẹ́ tó jẹ mọ́ nǹkan wọ̀nyí. Kí ẹ fi orúkọ yan ohun tí kálúku wọn á máa gbé. 33 Bí ìdílé àwọn ọmọ Mérárì+ á ṣe máa ṣiṣẹ́ nínú àgọ́ ìpàdé nìyí, kí Ítámárì ọmọ àlùfáà Áárónì+ máa darí wọn.”
34 Mósè àti Áárónì àti àwọn ìjòyè+ àpéjọ náà wá forúkọ àwọn ọmọ Kóhátì+ sílẹ̀ ní ìdílé-ìdílé àti agbo ilé bàbá wọn, 35 gbogbo àwọn tó jẹ́ ẹni ọgbọ̀n (30) ọdún sí àádọ́ta (50) ọdún, tí wọ́n wà lára àwọn tí a yàn pé kí wọ́n máa ṣiṣẹ́ nínú àgọ́ ìpàdé.+ 36 Gbogbo àwọn tí wọ́n forúkọ wọn sílẹ̀ ní ìdílé-ìdílé jẹ́ ẹgbẹ̀rún méjì ó lé ọgọ́rùn-ún méje àti àádọ́ta (2,750).+ 37 Èyí ni àwọn tí wọ́n forúkọ wọn sílẹ̀ nínú ìdílé àwọn ọmọ Kóhátì, gbogbo àwọn tó ń ṣiṣẹ́ nínú àgọ́ ìpàdé. Mósè àti Áárónì forúkọ wọn sílẹ̀ bí Jèhófà ṣe pa á láṣẹ nípasẹ̀ Mósè.+
38 Wọ́n forúkọ àwọn ọmọ Gẹ́ṣónì+ sílẹ̀ ní ìdílé-ìdílé àti agbo ilé bàbá wọn, 39 gbogbo àwọn tó jẹ́ ẹni ọgbọ̀n (30) ọdún sí àádọ́ta (50) ọdún, tí wọ́n wà lára àwọn tí a yàn pé kí wọ́n máa ṣiṣẹ́ nínú àgọ́ ìpàdé. 40 Gbogbo àwọn tí wọ́n forúkọ wọn sílẹ̀ ní ìdílé-ìdílé àti agbo ilé bàbá wọn jẹ́ ẹgbẹ̀rún méjì ó lé ọgọ́rùn-ún mẹ́fà àti ọgbọ̀n (2,630).+ 41 Bí wọ́n ṣe forúkọ ìdílé àwọn ọmọ Gẹ́ṣónì sílẹ̀ nìyí, gbogbo àwọn tó ń ṣiṣẹ́ nínú àgọ́ ìpàdé. Mósè àti Áárónì forúkọ wọn sílẹ̀ bí Jèhófà+ ṣe pa á láṣẹ.
42 Wọ́n forúkọ àwọn ọmọ Mérárì sílẹ̀ ní ìdílé-ìdílé àti agbo ilé bàbá wọn, 43 gbogbo àwọn tó jẹ́ ẹni ọgbọ̀n (30) ọdún sí àádọ́ta (50) ọdún, tí wọ́n wà lára àwọn tí a yàn pé kí wọ́n máa ṣiṣẹ́ nínú àgọ́ ìpàdé.+ 44 Gbogbo àwọn tí wọ́n forúkọ wọn sílẹ̀ ní ìdílé-ìdílé jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́ta ó lé igba (3,200).+ 45 Bí wọ́n ṣe forúkọ ìdílé àwọn ọmọ Mérárì sílẹ̀ nìyí, àwọn tí Mósè àti Áárónì forúkọ wọn sílẹ̀ bí Jèhófà ṣe pa á láṣẹ nípasẹ̀ Mósè.+
46 Mósè àti Áárónì àti àwọn ìjòyè Ísírẹ́lì forúkọ gbogbo àwọn ọmọ Léfì yìí sílẹ̀ ní ìdílé-ìdílé àti agbo ilé bàbá wọn; 47 wọ́n jẹ́ ẹni ọgbọ̀n (30) ọdún sí àádọ́ta (50) ọdún, gbogbo wọn ni a yàn láti máa ṣiṣẹ́, kí wọ́n sì máa gbé àwọn ẹrù tó jẹ mọ́ àgọ́ ìpàdé.+ 48 Gbogbo àwọn tí wọ́n forúkọ wọn sílẹ̀ jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́jọ ó lé ọgọ́rùn-ún márùn-ún àti ọgọ́rin (8,580).+ 49 Wọ́n forúkọ wọn sílẹ̀ bí Jèhófà ṣe pa á láṣẹ nípasẹ̀ Mósè, ní ìbámu pẹ̀lú iṣẹ́ tí wọ́n yàn fún kálukú àti ẹrù rẹ̀; wọ́n forúkọ wọn sílẹ̀ bí Jèhófà ṣe pa á láṣẹ fún Mósè.
5 Jèhófà wá sọ fún Mósè pé: 2 “Pàṣẹ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé kí wọ́n ní kí gbogbo adẹ́tẹ̀+ jáde kúrò nínú ibùdó àti gbogbo ẹni tí nǹkan ń dà lára rẹ̀+ pẹ̀lú gbogbo ẹni tí òkú èèyàn*+ ti sọ di aláìmọ́. 3 Ì báà jẹ́ ọkùnrin tàbí obìnrin, ṣe ni kí ẹ ní kí wọ́n jáde. Kí ẹ ní kí wọ́n lọ sí ẹ̀yìn ibùdó, kí wọ́n má bàa kó èérí bá+ àgọ́ àwọn tí mò ń gbé+ láàárín wọn.”* 4 Torí náà, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe bẹ́ẹ̀, wọ́n ní kí àwọn èèyàn náà lọ sí ẹ̀yìn ibùdó. Ohun tí Jèhófà sọ fún Mósè gẹ́lẹ́ ni àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe.
5 Jèhófà ń bá ọ̀rọ̀ tó ń sọ fún Mósè lọ pé: 6 “Sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé, ‘Tí ọkùnrin tàbí obìnrin kan bá dá èyíkéyìí nínú àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tí àwọn èèyàn ń dá, tó sì hùwà àìṣòótọ́ sí Jèhófà, ẹni* náà ti jẹ̀bi.+ 7 Ó* gbọ́dọ̀ jẹ́wọ́+ ẹ̀ṣẹ̀ tó* dá, kó san ohun tó jẹ̀bi rẹ̀ pa dà ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́, kó sì fi ìdá márùn-ún rẹ̀+ kún un; kó fún ẹni tó ṣe àìdáa sí. 8 Àmọ́ tí ẹni náà ò bá ní mọ̀lẹ́bí tó sún mọ́ ọn tó máa gba ohun tí ẹlẹ́ṣẹ̀ náà san dípò, kó dá a pa dà fún Jèhófà, yóò sì di ti àlùfáà, yàtọ̀ sí àgbò tó máa fi ṣe ètùtù fún un.+
9 “‘Kí gbogbo ọrẹ mímọ́ + tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì bá mú wá fún àlùfáà jẹ́ ti àlùfáà.+ 10 Àwọn ohun mímọ́ ti kálukú yóò máa jẹ́ tirẹ̀. Ohun yòówù tí kálukú bá fún àlùfáà yóò di ti àlùfáà.’”
11 Jèhófà ń bá ọ̀rọ̀ tó ń sọ fún Mósè lọ pé: 12 “Sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé, ‘Ohun tí ẹ máa ṣe nìyí tí ìyàwó ọkùnrin kan bá lọ hùwà tí kò tọ́, tó sì dalẹ̀ ọkọ rẹ̀, 13 tí ọkùnrin míì bá a+ sùn, àmọ́ tí ọkọ rẹ̀ ò mọ̀, tí àṣírí rẹ̀ kò tú, tí obìnrin náà sì sọ ara rẹ̀ di aláìmọ́ àmọ́ tí kò sí ẹni tó jẹ́rìí pé ó ṣe é, tí wọn ò sì ká a mọ́: 14 Tí ọkùnrin náà bá ń jowú, tó ń fura pé ìyàwó òun ti dalẹ̀ òun, tí obìnrin náà sì ti sọ ara rẹ̀ di aláìmọ́ tàbí tí ọkùnrin náà ń jowú, tó ń fura pé ìyàwó òun ti dalẹ̀ òun, àmọ́ tí obìnrin náà kò sọ ara rẹ̀ di aláìmọ́, 15 kí ọkùnrin náà mú ìyàwó rẹ̀ wá sọ́dọ̀ àlùfáà, kó mú ọrẹ dání fún un, ìyẹ̀fun ọkà bálì tó kún ìdá mẹ́wàá òṣùwọ̀n eéfà.* Kó má da òróró sí i, kó má sì fi oje igi tùràrí sórí rẹ̀, torí ọrẹ ọkà owú ni, ọrẹ ọkà tó ń múni rántí ẹ̀bi.
16 “‘Kí àlùfáà mú un wá síwájú, kó sì mú un dúró níwájú Jèhófà.+ 17 Kí àlùfáà bu omi mímọ́ sínú ohun èlò tí wọ́n fi amọ̀ ṣe, kí àlùfáà sì bù lára iyẹ̀pẹ̀ ilẹ̀ àgọ́ ìjọsìn, kó dà á sínú omi náà. 18 Kí àlùfáà mú kí obìnrin náà dúró níwájú Jèhófà, kó tú irun obìnrin náà, kó sì fi ọrẹ ọkà ìrántí sí àtẹ́lẹwọ́ obìnrin náà, ìyẹn ọrẹ ọkà owú,+ kí omi tó korò tó ń mú ègún+ wá sì wà lọ́wọ́ àlùfáà.
19 “‘Kí àlùfáà wá mú kó búra, kó sọ fún obìnrin náà pé: “Tí ọkùnrin kankan ò bá bá ọ sùn nígbà tí ọkọ rẹ ṣì ní àṣẹ+ lórí rẹ, tí o kò lọ hùwà tí kò tọ́, tí o kò sì di aláìmọ́, kí omi tó korò tó ń mú ègún wá yìí má ṣe ọ́ níbi. 20 Àmọ́ tí o bá ti lọ hùwà tí kò tọ́ nígbà tí ọkọ rẹ ṣì ní àṣẹ lórí rẹ, tí o sì fìyẹn sọ ara rẹ di aláìmọ́, tí o sì ti bá ọkùnrin míì+ tí kì í ṣe ọkọ rẹ sùn—” 21 Kí àlùfáà wá mú kí obìnrin náà búra, kó sì gégùn-ún nínú ìbúra náà, kí àlùfáà sọ fún obìnrin náà pé: “Kí Jèhófà ṣe ọ́ ní ẹni ègún àti ẹni ìbúra láàárín àwọn èèyàn rẹ, kí Jèhófà mú kí itan* rẹ joro,* kí ikùn rẹ sì wú. 22 Kí omi tó ń mú ègún wá yìí wọnú ìfun rẹ, kó sì mú kí ikùn rẹ wú, kí itan* rẹ sì joro.”* Kí obìnrin náà wá fèsì pé: “Àmín! Àmín!”*
23 “‘Lẹ́yìn náà, kí àlùfáà kọ àwọn ègún yìí sínú ìwé, kó sì fọ̀ ọ́ sínú omi tó korò náà. 24 Kó wá mú kí obìnrin náà mu omi tó korò tó ń mú ègún wá, omi tó ń mú ègún wá náà yóò wọnú rẹ̀, yóò sì korò. 25 Kí àlùfáà wá gba ọrẹ ọkà owú+ náà lọ́wọ́ obìnrin náà, kó fi ọrẹ ọkà náà síwá-sẹ́yìn níwájú Jèhófà, kó wá gbé e sún mọ́ pẹpẹ. 26 Kí àlùfáà bu ẹ̀kúnwọ́ ọrẹ ọkà náà láti fi ṣe ọrẹ ìṣàpẹẹrẹ, kó sì mú kó rú èéfín lórí pẹpẹ,+ lẹ́yìn náà, kó mú kí obìnrin náà mu omi náà. 27 Tó bá ti mú kí obìnrin náà mu omi náà, tí obìnrin náà bá ti sọ ara rẹ̀ di aláìmọ́, tó sì ti dalẹ̀ ọkọ rẹ̀, omi tó ń mú ègún wá náà yóò wọnú rẹ̀, yóò sì korò, ikùn rẹ̀ yóò wú, itan* rẹ̀ yóò sì joro,* obìnrin náà yóò sì di ẹni ègún láàárín àwọn èèyàn rẹ̀. 28 Àmọ́ tí obìnrin náà kò bá sọ ara rẹ̀ di ẹlẹ́gbin, tó sì mọ́, irú ìyà bẹ́ẹ̀ kò ní jẹ ẹ́, ó máa lè lóyún, á sì lè bímọ.
29 “‘Èyí ni òfin nípa owú,+ tí obìnrin kan bá lọ hùwà tí kò tọ́, tó sì sọ ara rẹ̀ di aláìmọ́ nígbà tí ọkọ rẹ̀ ṣì ní àṣẹ lórí rẹ̀, 30 tàbí tí ọkùnrin kan bá ń jowú, tó sì ń fura pé ìyàwó òun ti dalẹ̀ òun; kó mú kí ìyàwó rẹ̀ dúró níwájú Jèhófà, kí àlùfáà sì ṣe gbogbo ohun tí òfin yìí sọ fún obìnrin náà. 31 Ọkùnrin náà ò ní jẹ̀bi, àmọ́ ìyàwó rẹ̀ máa jìyà ohun tí òun fúnra rẹ̀ ṣe.’”
6 Jèhófà wá sọ fún Mósè pé: 2 “Sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé, ‘Tí ọkùnrin tàbí obìnrin kan bá jẹ́ ẹ̀jẹ́ pàtàkì pé òun fẹ́ di Násírì*+ fún Jèhófà, 3 kó yẹra fún wáìnì àti àwọn ohun mímu míì tó ní ọtí. Kó má mu ohun kíkan tí wọ́n fi wáìnì ṣe tàbí ohun kíkan tí wọ́n fi nǹkan tó ní ọtí+ ṣe. Kó má mu ohunkóhun tí wọ́n fi èso àjàrà ṣe, kó má sì jẹ èso àjàrà, ì báà jẹ́ tútù tàbí gbígbẹ. 4 Ní gbogbo ọjọ́ tó bá fi jẹ́ Násírì, kó má jẹ ohunkóhun tí wọ́n fi àjàrà ṣe, látorí èso àjàrà tí kò tíì pọ́n títí dórí èèpo rẹ̀.
5 “‘Ní gbogbo ọjọ́ tó bá fi jẹ́jẹ̀ẹ́ pé òun máa jẹ́ Násírì, kò gbọ́dọ̀ fi abẹ kan orí rẹ̀.+ Kó jẹ́ kí irun orí rẹ̀ gùn títí ọjọ́ tó fi ya ara rẹ̀ sọ́tọ̀ fún Jèhófà yóò fi pé, kó lè máa jẹ́ mímọ́. 6 Kò gbọ́dọ̀ sún mọ́* òkú èèyàn* ní gbogbo ọjọ́ tó bá fi ya ara rẹ̀ sọ́tọ̀ fún Jèhófà. 7 Ì báà jẹ́ bàbá rẹ̀, ìyá rẹ̀, arákùnrin rẹ̀ tàbí arábìnrin rẹ̀ ló kú, kò gbọ́dọ̀ sọ ara rẹ̀ di aláìmọ́,+ torí àmì wà ní orí rẹ̀ pé ó jẹ́ Násírì fún Ọlọ́run rẹ̀.
8 “‘Ní gbogbo ọjọ́ tó bá fi jẹ́ Násírì, ó jẹ́ mímọ́ sí Jèhófà. 9 Àmọ́ tí ẹnì kan bá dédé kú lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀,+ tó sì sọ irun rẹ̀ di aláìmọ́, irun tó fi hàn pé ó ya ara rẹ̀ sọ́tọ̀ fún Ọlọ́run,* ó gbọ́dọ̀ fá orí rẹ̀+ ní ọjọ́ tí wọ́n bá kéde pé ó ti di mímọ́. Kó fá a ní ọjọ́ keje. 10 Tó bá wá di ọjọ́ kẹjọ, kó mú ẹyẹ oriri méjì tàbí ọmọ ẹyẹlé méjì wá fún àlùfáà ní ẹnu ọ̀nà àgọ́ ìpàdé. 11 Kí àlùfáà fi ọ̀kan rú ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, kó fi èkejì rú ẹbọ sísun, kó sì ṣe ètùtù fún un torí ẹ̀ṣẹ̀+ tó dá tó jẹ mọ́ òkú* náà. Kó wá ya orí rẹ̀ sí mímọ́ ní ọjọ́ yẹn. 12 Kó tún ara rẹ̀ yà sọ́tọ̀ fún Jèhófà ní àwọn ọjọ́ tó fi jẹ́ Násírì, kó sì mú ọmọ àgbò ọlọ́dún kan wá láti fi rú ẹbọ ẹ̀bi. Àmọ́ kò ní ka àwọn ọjọ́ tó ti kọjá torí ó ti ba Násírì rẹ̀ jẹ́.
13 “‘Èyí ni òfin nípa Násírì: Tí ọjọ́ tó fi jẹ́ Násírì+ bá pé, kí ẹ mú un wá sí ẹnu ọ̀nà àgọ́ ìpàdé. 14 Ibẹ̀ ni kó mú ọrẹ rẹ̀ tó fẹ́ fún Jèhófà wá: ọmọ àgbò ọlọ́dún kan tí ara rẹ̀ dá ṣáṣá láti fi rú ẹbọ sísun,+ abo ọ̀dọ́ àgùntàn ọlọ́dún kan tí ara rẹ̀ dá ṣáṣá láti fi rú ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀,+ àgbò kan tí ara rẹ̀ dá ṣáṣá láti fi rú ẹbọ ìrẹ́pọ̀,+ 15 apẹ̀rẹ̀ búrẹ́dì aláìwú tó rí bí òrùka tí wọ́n fi ìyẹ̀fun tó kúnná ṣe, tí wọ́n pò mọ́ òróró, búrẹ́dì aláìwú pẹlẹbẹ tí wọ́n fi òróró pa àti ọrẹ ọkà+ wọn àti àwọn ọrẹ ohun mímu+ wọn. 16 Kí àlùfáà gbé e wá síwájú Jèhófà, kó fi rú ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ àti ẹbọ sísun. 17 Kó fi àgbò náà rúbọ gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ìrẹ́pọ̀ sí Jèhófà pẹ̀lú apẹ̀rẹ̀ búrẹ́dì aláìwú náà, kí àlùfáà sì mú ọrẹ ọkà+ àgbò náà àti ọrẹ ohun mímu rẹ̀ wá.
18 “‘Kí Násírì náà wá gé irun orí+ rẹ̀ tí kò gé rí* ní ẹnu ọ̀nà àgọ́ ìpàdé, kó kó irun náà jọ, èyí tó hù lórí rẹ̀ nígbà tó jẹ́ Násírì, kó kó o sínú iná tó wà lábẹ́ ẹbọ ìrẹ́pọ̀. 19 Kí àlùfáà sì mú apá àgbò náà tí wọ́n bọ̀,+ kó mú búrẹ́dì aláìwú kan tó rí bí òrùka látinú apẹ̀rẹ̀ náà àti búrẹ́dì aláìwú pẹlẹbẹ kan, kó sì kó o lé àtẹ́lẹwọ́ Násírì náà lẹ́yìn tó ti gé àmì Násírì rẹ̀ kúrò. 20 Kí àlùfáà sì fì wọ́n síwá-sẹ́yìn bí ọrẹ fífì níwájú Jèhófà.+ Ohun mímọ́ ló jẹ́ fún àlùfáà, pẹ̀lú igẹ̀ ọrẹ fífì àti ẹsẹ̀ ọrẹ+ náà. Lẹ́yìn náà, Násírì náà lè mu wáìnì.
21 “‘Èyí ni òfin nípa Násírì+ tó jẹ́jẹ̀ẹ́: Tó bá jẹ́jẹ̀ẹ́, tí agbára rẹ̀ sì gbé e láti ṣe ọrẹ fún Jèhófà, ọrẹ tó pọ̀ jù ohun tí a béèrè lọ́wọ́ Násírì, kó san ẹ̀jẹ́ rẹ̀ kó lè tẹ̀ lé òfin Násírì.’”
22 Jèhófà sọ fún Mósè pé: 23 “Sọ fún Áárónì àti àwọn ọmọ rẹ̀ pé, ‘Bí ẹ ó ṣe máa súre+ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nìyí. Kí ẹ sọ fún wọn pé:
24 “Kí Jèhófà bù kún ọ,+ kó sì pa ọ́ mọ́.
25 Kí Jèhófà mú kí ojú rẹ̀ tàn sí ọ+ lára, kó sì ṣojúure sí ọ.
26 Kí Jèhófà bojú wò ọ́, kó sì fún ọ ní àlàáfíà.”’+
27 Kí wọ́n sì fi orúkọ mi sára àwọn ọmọ Ísírẹ́lì,+ kí n lè bù kún wọn.”+
7 Ní ọjọ́ tí Mósè to àgọ́ ìjọsìn+ náà tán, ó fòróró yàn án,+ ó sì yà á sí mímọ́ pẹ̀lú gbogbo ohun tó wà níbẹ̀, pẹpẹ àti gbogbo ohun èlò rẹ̀.+ Lẹ́yìn tó fòróró yan nǹkan wọ̀nyí, tó sì sọ wọ́n di mímọ́,+ 2 àwọn ìjòyè Ísírẹ́lì,+ àwọn olórí agbo ilé bàbá wọn mú ọrẹ wá. Àwọn ìjòyè yìí látinú àwọn ẹ̀yà, tí wọ́n darí ìforúkọsílẹ̀ náà 3 mú ọrẹ wọn wá síwájú Jèhófà, kẹ̀kẹ́ ẹrù mẹ́fà tí wọ́n bò àti màlúù méjìlá (12), kẹ̀kẹ́ ẹrù kan fún ìjòyè méjì àti akọ màlúù* kan fún ẹnì kọ̀ọ̀kan; wọ́n sì kó o wá síwájú àgọ́ ìjọsìn. 4 Jèhófà sọ fún Mósè pé: 5 “Gba nǹkan wọ̀nyí lọ́wọ́ wọn, torí wọ́n máa fi ṣiṣẹ́ ní àgọ́ ìpàdé, kí o sì fún àwọn ọmọ Léfì, kí o fún kálukú ní ohun tó máa nílò láti fi ṣiṣẹ́ rẹ̀.”
6 Mósè wá gba àwọn kẹ̀kẹ́ ẹrù àti màlúù náà, ó sì kó o fún àwọn ọmọ Léfì. 7 Ó fún àwọn ọmọ Gẹ́ṣónì ní kẹ̀kẹ́ ẹrù méjì àti màlúù mẹ́rin, bí wọ́n ṣe nílò rẹ̀ fún iṣẹ́+ wọn; 8 ó sì fún àwọn ọmọ Mérárì ní kẹ̀kẹ́ ẹrù mẹ́rin àti màlúù mẹ́jọ, bí wọ́n ṣe nílò rẹ̀ fún iṣẹ́ wọn, Ítámárì ọmọ àlùfáà Áárónì+ ló ń darí wọn. 9 Àmọ́ kò fún àwọn ọmọ Kóhátì ní ìkankan, torí ojúṣe wọn jẹ mọ́ iṣẹ́ ibi mímọ́,+ èjìká+ ni wọ́n sì máa ń fi ru àwọn ohun mímọ́.
10 Àwọn ìjòyè náà wá mú ọrẹ wọn wá síbi ìyàsímímọ́*+ pẹpẹ lọ́jọ́ tí wọ́n fòróró yàn án. Nígbà tí àwọn ìjòyè náà mú ọrẹ wọn wá síwájú pẹpẹ, 11 Jèhófà sọ fún Mósè pé: “Ní ọjọ́ kọ̀ọ̀kan, kí ìjòyè kọ̀ọ̀kan mú ọrẹ rẹ̀ wá fún ìyàsímímọ́ pẹpẹ náà, ní ọjọ́ kan tẹ̀ lé òmíràn.”
12 Ní ọjọ́ kìíní, Náṣónì+ ọmọ Ámínádábù láti ẹ̀yà Júdà mú ọrẹ rẹ̀ wá. 13 Ọrẹ tó mú wá ni abọ́ ìjẹun fàdákà kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ àádóje (130) ṣékélì* àti abọ́ fàdákà kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ àádọ́rin (70) ṣékélì, ó jẹ́ ìwọ̀n ṣékélì ibi mímọ́,*+ ìyẹ̀fun tó kúnná tí wọ́n pò mọ́ òróró kún inú méjèèjì, láti fi ṣe ọrẹ ọkà;+ 14 ife wúrà* kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ ṣékélì mẹ́wàá, tí tùràrí kún inú rẹ̀; 15 akọ ọmọ màlúù kan, àgbò kan, akọ ọ̀dọ́ àgùntàn kan tó jẹ́ ọlọ́dún kan láti fi rú ẹbọ sísun;+ 16 ọmọ ewúrẹ́ kan láti fi rú ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀;+ 17 àti màlúù méjì, àgbò márùn-ún, òbúkọ márùn-ún àti akọ ọ̀dọ́ àgùntàn márùn-ún tí ọ̀kọ̀ọ̀kan jẹ́ ọlọ́dún kan láti fi rú ẹbọ ìrẹ́pọ̀.+ Èyí ni ọrẹ tí Náṣónì ọmọ Ámínádábù+ mú wá.
18 Ní ọjọ́ kejì, Nétánélì+ ọmọ Súárì, ìjòyè Ísákà mú ọrẹ wá. 19 Ọrẹ tó mú wá ni abọ́ ìjẹun fàdákà kan, tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ àádóje (130) ṣékélì àti abọ́ fàdákà kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ àádọ́rin (70) ṣékélì, ó jẹ́ ìwọ̀n ṣékélì ibi mímọ́,+ ìyẹ̀fun tó kúnná tí wọ́n pò mọ́ òróró kún inú méjèèjì, láti fi ṣe ọrẹ ọkà;+ 20 ife wúrà kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ ṣékélì mẹ́wàá, tí tùràrí kún inú rẹ̀; 21 akọ ọmọ màlúù kan, àgbò kan àti akọ ọ̀dọ́ àgùntàn kan tó jẹ́ ọlọ́dún kan, láti fi rú ẹbọ sísun;+ 22 ọmọ ewúrẹ́ kan láti fi rú ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀;+ 23 àti màlúù méjì, àgbò márùn-ún, òbúkọ márùn-ún àti akọ ọ̀dọ́ àgùntàn márùn-ún tí ọ̀kọ̀ọ̀kan jẹ́ ọlọ́dún kan láti fi rú ẹbọ ìrẹ́pọ̀.+ Èyí ni ọrẹ tí Nétánélì ọmọ Súárì mú wá.
24 Ní ọjọ́ kẹta, Élíábù+ ọmọ Hélónì, ìjòyè àwọn ọmọ Sébúlúnì, 25 mú ọrẹ wá, ọrẹ tó mú wá ni abọ́ ìjẹun fàdákà kan, tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ àádóje (130) ṣékélì àti abọ́ fàdákà kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ àádọ́rin (70) ṣékélì, ó jẹ́ ìwọ̀n ṣékélì ibi mímọ́,+ ìyẹ̀fun tó kúnná tí wọ́n pò mọ́ òróró kún inú méjèèjì, láti fi ṣe ọrẹ ọkà;+ 26 ife wúrà kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ ṣékélì mẹ́wàá, tí tùràrí kún inú rẹ̀; 27 akọ ọmọ màlúù kan, àgbò kan àti akọ ọ̀dọ́ àgùntàn kan tó jẹ́ ọlọ́dún kan, láti fi rú ẹbọ sísun;+ 28 ọmọ ewúrẹ́ kan láti fi rú ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀;+ 29 àti màlúù méjì, àgbò márùn-ún, òbúkọ márùn-ún àti akọ ọ̀dọ́ àgùntàn márùn-ún tí ọ̀kọ̀ọ̀kan jẹ́ ọlọ́dún kan láti fi rú ẹbọ ìrẹ́pọ̀.+ Èyí ni ọrẹ tí Élíábù+ ọmọ Hélónì mú wá.
30 Ní ọjọ́ kẹrin, Élísúrì+ ọmọ Ṣédéúrì, ìjòyè àwọn ọmọ Rúbẹ́nì 31 mú ọrẹ wá, ọrẹ tó mú wá ni abọ́ ìjẹun fàdákà kan, tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ àádóje (130) ṣékélì àti abọ́ fàdákà kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ àádọ́rin (70) ṣékélì, ó jẹ́ ìwọ̀n ṣékélì ibi mímọ́,+ ìyẹ̀fun tó kúnná tí wọ́n pò mọ́ òróró kún inú méjèèjì, láti fi ṣe ọrẹ ọkà;+ 32 ife wúrà kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ ṣékélì mẹ́wàá, tí tùràrí kún inú rẹ̀; 33 akọ ọmọ màlúù kan, àgbò kan àti akọ ọ̀dọ́ àgùntàn kan tó jẹ́ ọlọ́dún kan, láti fi rú ẹbọ sísun;+ 34 ọmọ ewúrẹ́ kan láti fi rú ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀;+ 35 àti màlúù méjì, àgbò márùn-ún, òbúkọ márùn-ún àti akọ ọ̀dọ́ àgùntàn márùn-ún tí ọ̀kọ̀ọ̀kan jẹ́ ọlọ́dún kan láti fi rú ẹbọ ìrẹ́pọ̀.+ Èyí ni ọrẹ tí Élísúrì+ ọmọ Ṣédéúrì mú wá.
36 Ní ọjọ́ karùn-ún, Ṣẹ́lúmíẹ́lì+ ọmọ Súríṣádáì, ìjòyè àwọn ọmọ Síméónì, 37 mú ọrẹ wá, ọrẹ tó mú wá ni abọ́ ìjẹun fàdákà kan, tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ àádóje (130) ṣékélì àti abọ́ fàdákà kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ àádọ́rin (70) ṣékélì, ó jẹ́ ìwọ̀n ṣékélì ibi mímọ́,+ ìyẹ̀fun tó kúnná tí wọ́n pò mọ́ òróró kún inú méjèèjì, láti fi ṣe ọrẹ ọkà;+ 38 ife wúrà kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ ṣékélì mẹ́wàá, tí tùràrí kún inú rẹ̀; 39 akọ ọmọ màlúù kan, àgbò kan àti akọ ọ̀dọ́ àgùntàn kan tó jẹ́ ọlọ́dún kan, láti fi rú ẹbọ sísun;+ 40 ọmọ ewúrẹ́ kan láti fi rú ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀;+ 41 àti màlúù méjì, àgbò márùn-ún, òbúkọ márùn-ún àti akọ ọ̀dọ́ àgùntàn márùn-ún tí ọ̀kọ̀ọ̀kan jẹ́ ọlọ́dún kan láti fi rú ẹbọ ìrẹ́pọ̀.+ Èyí ni ọrẹ tí Ṣẹ́lúmíẹ́lì+ ọmọ Súríṣádáì mú wá.
42 Ní ọjọ́ kẹfà, Élíásáfù+ ọmọ Déúélì, ìjòyè àwọn ọmọ Gádì 43 mú ọrẹ wá, ọrẹ tó mú wá ni abọ́ ìjẹun fàdákà kan, tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ àádóje (130) ṣékélì àti abọ́ fàdákà kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ àádọ́rin (70) ṣékélì, ó jẹ́ ìwọ̀n ṣékélì ibi mímọ́,+ ìyẹ̀fun tó kúnná tí wọ́n pò mọ́ òróró kún inú méjèèjì, láti fi ṣe ọrẹ ọkà;+ 44 ife wúrà kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ ṣékélì mẹ́wàá, tí tùràrí kún inú rẹ̀; 45 akọ ọmọ màlúù kan, àgbò kan àti akọ ọ̀dọ́ àgùntàn kan tó jẹ́ ọlọ́dún kan, láti fi rú ẹbọ sísun;+ 46 ọmọ ewúrẹ́ kan láti fi rú ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀;+ 47 àti màlúù méjì, àgbò márùn-ún, òbúkọ márùn-ún àti akọ ọ̀dọ́ àgùntàn márùn-ún tí ọ̀kọ̀ọ̀kan jẹ́ ọlọ́dún kan láti fi rú ẹbọ ìrẹ́pọ̀.+ Èyí ni ọrẹ tí Élíásáfù+ ọmọ Déúélì mú wá.
48 Ní ọjọ́ keje, Élíṣámà+ ọmọ Ámíhúdù, ìjòyè àwọn ọmọ Éfúrémù 49 mú ọrẹ wá, ọrẹ tó mú wá ni abọ́ ìjẹun fàdákà kan, tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ àádóje (130) ṣékélì àti abọ́ fàdákà kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ àádọ́rin (70) ṣékélì, ó jẹ́ ìwọ̀n ṣékélì ibi mímọ́,+ ìyẹ̀fun tó kúnná tí wọ́n pò mọ́ òróró kún inú méjèèjì, láti fi ṣe ọrẹ ọkà;+ 50 ife wúrà kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ ṣékélì mẹ́wàá, tí tùràrí kún inú rẹ̀; 51 akọ ọmọ màlúù kan, àgbò kan àti akọ ọ̀dọ́ àgùntàn kan tó jẹ́ ọlọ́dún kan, láti fi rú ẹbọ sísun;+ 52 ọmọ ewúrẹ́ kan láti fi rú ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀;+ 53 àti màlúù méjì, àgbò márùn-ún, òbúkọ márùn-ún àti akọ ọ̀dọ́ àgùntàn márùn-ún tí ọ̀kọ̀ọ̀kan jẹ́ ọlọ́dún kan láti fi rú ẹbọ ìrẹ́pọ̀.+ Èyí ni ọrẹ tí Élíṣámà+ ọmọ Ámíhúdù mú wá.
54 Ní ọjọ́ kẹjọ, Gàmálíẹ́lì+ ọmọ Pédásúrì, ìjòyè àwọn ọmọ Mánásè 55 mú ọrẹ wá, ọrẹ tó mú wá ni abọ́ ìjẹun fàdákà kan, tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ àádóje (130) ṣékélì àti abọ́ fàdákà kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ àádọ́rin (70) ṣékélì, ó jẹ́ ìwọ̀n ṣékélì ibi mímọ́,+ ìyẹ̀fun tó kúnná tí wọ́n pò mọ́ òróró kún inú méjèèjì, láti fi ṣe ọrẹ ọkà;+ 56 ife wúrà kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ ṣékélì mẹ́wàá, tí tùràrí kún inú rẹ̀; 57 akọ ọmọ màlúù kan, àgbò kan àti akọ ọ̀dọ́ àgùntàn kan tó jẹ́ ọlọ́dún kan láti fi rú ẹbọ sísun;+ 58 ọmọ ewúrẹ́ kan láti fi rú ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀;+ 59 àti màlúù méjì, àgbò márùn-ún, òbúkọ márùn-ún àti akọ ọ̀dọ́ àgùntàn márùn-ún tí ọ̀kọ̀ọ̀kan jẹ́ ọlọ́dún kan láti fi rú ẹbọ ìrẹ́pọ̀.+ Èyí ni ọrẹ tí Gàmálíẹ́lì+ ọmọ Pédásúrì mú wá.
60 Ní ọjọ́ kẹsàn-án, Ábídánì+ ọmọ Gídéónì, ìjòyè+ àwọn ọmọ Bẹ́ńjámínì 61 mú ọrẹ wá, ọrẹ tó mú wá ni abọ́ ìjẹun fàdákà kan, tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ àádóje (130) ṣékélì àti abọ́ fàdákà kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ àádọ́rin (70) ṣékélì, ó jẹ́ ìwọ̀n ṣékélì ibi mímọ́,+ ìyẹ̀fun tó kúnná tí wọ́n pò mọ́ òróró kún inú méjèèjì, láti fi ṣe ọrẹ ọkà;+ 62 ife wúrà kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ ṣékélì mẹ́wàá, tí tùràrí kún inú rẹ̀; 63 akọ ọmọ màlúù kan, àgbò kan àti akọ ọ̀dọ́ àgùntàn kan tó jẹ́ ọlọ́dún kan, láti fi rú ẹbọ sísun;+ 64 ọmọ ewúrẹ́ kan láti fi rú ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀;+ 65 àti màlúù méjì, àgbò márùn-ún, òbúkọ márùn-ún àti akọ ọ̀dọ́ àgùntàn márùn-ún tí ọ̀kọ̀ọ̀kan jẹ́ ọlọ́dún kan láti fi rú ẹbọ ìrẹ́pọ̀.+ Èyí ni ọrẹ tí Ábídánì+ ọmọ Gídéónì mú wá.
66 Ní ọjọ́ kẹwàá, Áhíésérì+ ọmọ Ámíṣádáì, ìjòyè àwọn ọmọ Dánì 67 mú ọrẹ wá, ọrẹ tó mú wá ni abọ́ ìjẹun fàdákà kan, tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ àádóje (130) ṣékélì àti abọ́ fàdákà kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ àádọ́rin (70) ṣékélì, ó jẹ́ ìwọ̀n ṣékélì ibi mímọ́,+ ìyẹ̀fun tó kúnná tí wọ́n pò mọ́ òróró kún inú méjèèjì, láti fi ṣe ọrẹ ọkà;+ 68 ife wúrà kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ ṣékélì mẹ́wàá, tí tùràrí kún inú rẹ̀; 69 akọ ọmọ màlúù kan, àgbò kan àti akọ ọ̀dọ́ àgùntàn kan tó jẹ́ ọlọ́dún kan, láti fi rú ẹbọ sísun;+ 70 ọmọ ewúrẹ́ kan láti fi rú ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀;+ 71 àti màlúù méjì, àgbò márùn-ún, òbúkọ márùn-ún àti akọ ọ̀dọ́ àgùntàn márùn-ún tí ọ̀kọ̀ọ̀kan jẹ́ ọlọ́dún kan láti fi rú ẹbọ ìrẹ́pọ̀.+ Èyí ni ọrẹ tí Áhíésérì+ ọmọ Ámíṣádáì mú wá.
72 Ní ọjọ́ kọkànlá, Págíẹ́lì+ ọmọ Ókíránì, ìjòyè àwọn ọmọ Áṣérì 73 mú ọrẹ wá, ọrẹ tó mú wá ni abọ́ ìjẹun fàdákà kan, tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ àádóje (130) ṣékélì àti abọ́ fàdákà kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ àádọ́rin (70) ṣékélì, ó jẹ́ ìwọ̀n ṣékélì ibi mímọ́,+ ìyẹ̀fun tó kúnná tí wọ́n pò mọ́ òróró kún inú méjèèjì, láti fi ṣe ọrẹ ọkà;+ 74 ife wúrà kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ ṣékélì mẹ́wàá, tí tùràrí kún inú rẹ̀; 75 akọ ọmọ màlúù kan, àgbò kan àti akọ ọ̀dọ́ àgùntàn kan tó jẹ́ ọlọ́dún kan, láti fi rú ẹbọ sísun;+ 76 ọmọ ewúrẹ́ kan láti fi rú ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀;+ 77 àti màlúù méjì, àgbò márùn-ún, òbúkọ márùn-ún àti akọ ọ̀dọ́ àgùntàn márùn-ún tí ọ̀kọ̀ọ̀kan jẹ́ ọlọ́dún kan láti fi rú ẹbọ ìrẹ́pọ̀.+ Èyí ni ọrẹ tí Págíẹ́lì+ ọmọ Ókíránì mú wá.
78 Ní ọjọ́ kejìlá, Áhírà+ ọmọ Énánì, ìjòyè àwọn ọmọ Náfútálì 79 mú ọrẹ wá, ọrẹ tó mú wá ni abọ́ ìjẹun fàdákà kan, tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ àádóje (130) ṣékélì àti abọ́ fàdákà kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ àádọ́rin (70) ṣékélì, ó jẹ́ ìwọ̀n ṣékélì ibi mímọ́,+ ìyẹ̀fun tó kúnná tí wọ́n pò mọ́ òróró kún inú méjèèjì, láti fi ṣe ọrẹ ọkà;+ 80 ife wúrà kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ ṣékélì mẹ́wàá, tí tùràrí kún inú rẹ̀; 81 akọ ọmọ màlúù kan, àgbò kan àti akọ ọ̀dọ́ àgùntàn kan tó jẹ́ ọlọ́dún kan, láti fi rú ẹbọ sísun;+ 82 ọmọ ewúrẹ́ kan láti fi rú ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀;+ 83 àti màlúù méjì, àgbò márùn-ún, òbúkọ márùn-ún àti akọ ọ̀dọ́ àgùntàn márùn-ún tí ọ̀kọ̀ọ̀kan jẹ́ ọlọ́dún kan láti fi rú ẹbọ ìrẹ́pọ̀.+ Èyí ni ọrẹ tí Áhírà+ ọmọ Énánì mú wá.
84 Èyí ni ọrẹ+ tí àwọn ìjòyè Ísírẹ́lì mú wá síbi ìyàsímímọ́ pẹpẹ nígbà tí wọ́n fòróró yàn án: abọ́ ìjẹun méjìlá (12) tí wọ́n fi fàdákà ṣe, abọ́ fàdákà méjìlá (12), ife wúrà méjìlá (12);+ 85 ìwọ̀n abọ́ ìjẹun kọ̀ọ̀kan tí wọ́n fi fàdákà ṣe jẹ́ àádóje (130) ṣékélì, ìwọ̀n abọ́ kọ̀ọ̀kan sì jẹ́ àádọ́rin (70) ṣékélì, gbogbo fàdákà tí wọ́n fi ṣe àwọn ohun èlò náà jẹ́ ẹgbẹ̀rún méjì ó lé ọgọ́rùn-ún mẹ́rin (2,400) ṣékélì, ó jẹ́ ìwọ̀n ṣékélì ibi mímọ́;+ 86 ìwọ̀n ọ̀kọ̀ọ̀kan ife wúrà méjìlá (12) náà tí tùràrí kún inú rẹ̀ jẹ́ ṣékélì mẹ́wàá, ó jẹ́ ìwọ̀n ṣékélì ibi mímọ́, gbogbo wúrà àwọn ife náà jẹ́ ọgọ́fà (120) ṣékélì. 87 Gbogbo ẹran tí wọ́n fi rú ẹbọ sísun jẹ́ akọ màlúù méjìlá (12), àgbò méjìlá (12), akọ ọ̀dọ́ àgùntàn méjìlá (12) tí ọ̀kọ̀ọ̀kan jẹ́ ọlọ́dún kan àti àwọn ọrẹ ọkà wọn àti ọmọ ewúrẹ́ méjìlá (12) tí wọ́n fi rú ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀; 88 gbogbo ẹran tí wọ́n fi rú ẹbọ ìrẹ́pọ̀ jẹ́ akọ màlúù mẹ́rìnlélógún (24), ọgọ́ta (60) àgbò, ọgọ́ta (60) òbúkọ àti ọgọ́ta (60) akọ ọ̀dọ́ àgùntàn tí ọ̀kọ̀ọ̀kan jẹ́ ọlọ́dún kan. Èyí ni ọrẹ+ tí wọ́n mú wá síbi ìyàsímímọ́ pẹpẹ lẹ́yìn tí wọ́n fòróró yàn án.+
89 Nígbàkigbà tí Mósè bá lọ sínú àgọ́ ìpàdé láti bá Ọlọ́run*+ sọ̀rọ̀, ó máa ń gbọ́ ohùn tó ń bá a sọ̀rọ̀ láti òkè ìbòrí+ àpótí Ẹ̀rí, láàárín àwọn kérúbù+ méjèèjì; Ọlọ́run á sì bá a sọ̀rọ̀.
8 Jèhófà sọ fún Mósè pé: 2 “Sọ fún Áárónì pé, ‘Tí o bá tan àwọn fìtílà, kí fìtílà méje mọ́lẹ̀ síwájú ọ̀pá fìtílà+ náà.’” 3 Ohun tí Áárónì sì ṣe nìyí: Ó tan àwọn fìtílà rẹ̀ kó lè mọ́lẹ̀ síwájú ọ̀pá fìtílà+ náà, bí Jèhófà ṣe pa á láṣẹ fún Mósè. 4 Bí wọ́n ṣe ṣe ọ̀pá fìtílà náà nìyí: Wúrà tí wọ́n fi òòlù lù ni wọ́n fi ṣe é; òòlù ni wọ́n fi lù ú+ láti ibi ọ̀pá rẹ̀ débi àwọn ìtànná rẹ̀. Wọ́n ṣe ọ̀pá fìtílà náà bó ṣe rí nínú ìran+ tí Jèhófà fi han Mósè.
5 Jèhófà tún sọ fún Mósè pé: 6 “Mú àwọn ọmọ Léfì láàárín àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, kí o sì wẹ̀ wọ́n mọ́.+ 7 Bí o ṣe máa wẹ̀ wọ́n mọ́ nìyí: Wọ́n omi ìwẹ̀mọ́ ẹ̀ṣẹ̀ sí wọn lára, kí wọ́n sì fi abẹ fá gbogbo irun ara wọn, kí wọ́n fọ aṣọ wọn, kí wọ́n sì wẹ ara wọn mọ́.+ 8 Kí wọ́n wá mú akọ ọmọ màlúù+ kan àti ọrẹ ọkà+ rẹ̀ tó jẹ́ ìyẹ̀fun tó kúnná tí wọ́n pò mọ́ òróró, kí o sì mú akọ ọmọ màlúù míì láti fi rú ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀.+ 9 Kí o mú àwọn ọmọ Léfì wá síwájú àgọ́ ìpàdé, kí o sì kó gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì+ jọ. 10 Tí o bá mú àwọn ọmọ Léfì wá síwájú Jèhófà, kí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì gbé ọwọ́ wọn lé àwọn ọmọ Léfì.+ 11 Kí Áárónì mú àwọn ọmọ Léfì wá* síwájú Jèhófà gẹ́gẹ́ bí ọrẹ fífì+ láti ọwọ́ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, kí wọ́n sì máa ṣiṣẹ́ Jèhófà.+
12 “Kí àwọn ọmọ Léfì gbé ọwọ́ wọn lé orí àwọn akọ màlúù+ náà. Lẹ́yìn náà, kí wọ́n fi ọ̀kan rú ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, kí wọ́n sì fi ìkejì rú ẹbọ sísun sí Jèhófà láti ṣe ètùtù+ fún àwọn ọmọ Léfì. 13 Kí o mú kí àwọn ọmọ Léfì dúró níwájú Áárónì àti àwọn ọmọ rẹ̀, kí o sì mú wọn wá* fún Jèhófà bí ọrẹ fífì. 14 Kí o ya àwọn ọmọ Léfì sọ́tọ̀ kúrò lára àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, àwọn ọmọ Léfì yóò sì di tèmi.+ 15 Lẹ́yìn náà, kí àwọn ọmọ Léfì wọlé, kí wọ́n sì máa ṣiṣẹ́ ní àgọ́ ìpàdé. Bí o ṣe máa wẹ̀ wọ́n mọ́ nìyí, tí wàá sì mú wọn wá* bí ọrẹ fífì. 16 Àwọn ni a fi fúnni, a fún mi látinú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì. Èmi yóò mú wọn fún ara mi dípò gbogbo àkọ́bí* àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.+ 17 Torí tèmi ni gbogbo àkọ́bí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, ì báà jẹ́ èèyàn tàbí ẹranko.+ Ọjọ́ tí mo pa gbogbo àkọ́bí ní ilẹ̀ Íjíbítì+ ni mo yà wọ́n sí mímọ́ fún ara mi. 18 Èmi yóò mú àwọn ọmọ Léfì dípò gbogbo àkọ́bí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì. 19 Èmi yóò fún Áárónì àti àwọn ọmọ rẹ̀ ní àwọn ọmọ Léfì bí àwọn tí a fi fúnni láàárín àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, kí wọ́n lè máa ṣiṣẹ́ nínú àgọ́ ìpàdé+ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, kí wọ́n sì máa ṣe ètùtù fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì,+ kí ìyọnu má bàa dé bá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì torí wọ́n sún mọ́ ibi mímọ́.”
20 Ohun tí Mósè àti Áárónì àti gbogbo àpéjọ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe fún àwọn ọmọ Léfì nìyẹn. Gbogbo ohun tí Jèhófà pa láṣẹ fún Mósè nípa àwọn ọmọ Léfì ni àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe gẹ́lẹ́. 21 Àwọn ọmọ Léfì wẹ ara wọn mọ́, wọ́n sì fọ aṣọ+ wọn. Lẹ́yìn náà, Áárónì mú wọn wá* síwájú Jèhófà+ bí ọrẹ fífì. Áárónì wá ṣe ètùtù fún wọn kó lè wẹ̀ wọ́n mọ́.+ 22 Lẹ́yìn náà, àwọn ọmọ Léfì wọlé kí wọ́n lè máa ṣe iṣẹ́ wọn nínú àgọ́ ìpàdé níwájú Áárónì àti àwọn ọmọ rẹ̀. Ohun tí Jèhófà pa láṣẹ fún Mósè nípa àwọn ọmọ Léfì ni wọ́n ṣe fún wọn gẹ́lẹ́.
23 Jèhófà wá sọ fún Mósè pé: 24 “Èyí kan àwọn ọmọ Léfì: Kí ẹni tó bá ti pé ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n (25) tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ dara pọ̀ mọ́ àwọn tó ń ṣiṣẹ́ nínú àgọ́ ìpàdé. 25 Àmọ́ tó bá ti lé ní ẹni àádọ́ta (50) ọdún, kó fẹ̀yìn tì lẹ́nu iṣẹ́ náà, kó sì ṣíwọ́ iṣẹ́. 26 Ó lè máa ṣèrànwọ́ fún àwọn arákùnrin rẹ̀ tí wọ́n ń ṣe ojúṣe wọn nínú àgọ́ ìpàdé, àmọ́ kó má ṣiṣẹ́ níbẹ̀. Ohun tí o máa ṣe nípa àwọn ọmọ Léfì àti ojúṣe+ wọn nìyí.”
9 Jèhófà bá Mósè sọ̀rọ̀ ní aginjù Sínáì ní oṣù kìíní,+ ọdún kejì tí wọ́n kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì, ó sọ pé: 2 “Kí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣètò ẹbọ+ Ìrékọjá ní àkókò rẹ̀.+ 3 Ìrọ̀lẹ́* ọjọ́ kẹrìnlá oṣù yìí ni kí ẹ ṣètò rẹ̀ ní àkókò rẹ̀. Kí ẹ tẹ̀ lé gbogbo àṣẹ rẹ̀ àti ìlànà tó wà fún un tí ẹ bá ń ṣètò rẹ̀.”+
4 Mósè wá sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé kí wọ́n ṣètò ẹbọ Ìrékọjá. 5 Ní ìrọ̀lẹ́* ọjọ́ kẹrìnlá oṣù kìíní, wọ́n ṣètò ẹbọ Ìrékọjá náà ní aginjù Sínáì. Gbogbo ohun tí Jèhófà pa láṣẹ fún Mósè ni àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe.
6 Ó ṣẹlẹ̀ pé àwọn ọkùnrin kan di aláìmọ́ torí wọ́n fara kan òkú èèyàn,*+ wọn ò wá lè ṣètò ẹbọ Ìrékọjá ní ọjọ́ yẹn. Torí náà, àwọn ọkùnrin náà wá sọ́dọ̀ Mósè àti Áárónì ní ọjọ́ yẹn,+ 7 wọ́n sì sọ fún un pé: “A ti di aláìmọ́ torí a fara kan òkú èèyàn.* Kí ló dé tí a kò fi lè mú ọrẹ náà wá fún Jèhófà láàárín àwọn ọmọ Ísírẹ́lì+ ní àkókò rẹ̀?” 8 Ni Mósè bá dá wọn lóhùn pé: “Ẹ dúró ná, ẹ jẹ́ kí n gbọ́ ohun tí Jèhófà máa sọ nípa yín.”+
9 Jèhófà wá sọ fún Mósè pé: 10 “Sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé, ‘Tí ẹnikẹ́ni nínú yín tàbí nínú àwọn ìran yín tó ń bọ̀ bá di aláìmọ́ torí pé ó fara kan òkú èèyàn*+ tàbí tí ó rin ìrìn àjò ọ̀nà jíjìn, ẹni náà ṣì gbọ́dọ̀ ṣètò ẹbọ Ìrékọjá fún Jèhófà. 11 Kí wọ́n ṣètò rẹ̀ ní ìrọ̀lẹ́* ọjọ́ kẹrìnlá oṣù kejì.+ Kí wọ́n jẹ ẹ́ pẹ̀lú búrẹ́dì aláìwú àti ewébẹ̀ kíkorò.+ 12 Wọn ò gbọ́dọ̀ ṣẹ́ ìkankan lára rẹ̀ kù di àárọ̀,+ wọn ò sì gbọ́dọ̀ fọ́ ìkankan nínú egungun rẹ̀.+ Kí wọ́n tẹ̀ lé gbogbo àṣẹ tó wà fún Ìrékọjá láti ṣètò rẹ̀. 13 Àmọ́ tí ẹnì kan bá wà ní mímọ́ tàbí tí kò rìnrìn àjò, tó sì kọ̀ láti ṣètò ẹbọ Ìrékọjá, ṣe ni kí ẹ pa ẹni* náà, kí ẹ lè mú un kúrò láàárín àwọn èèyàn rẹ̀,+ torí kò mú ọrẹ Jèhófà wá ní àkókò rẹ̀. Ẹni náà yóò jìyà ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀.
14 “‘Tí àjèjì kan bá ń gbé lọ́dọ̀ yín, kí òun náà ṣètò ẹbọ Ìrékọjá fún Jèhófà.+ Kó tẹ̀ lé àṣẹ àti ìlànà tó wà fún Ìrékọjá láti ṣètò rẹ̀.+ Àṣẹ kan náà ni kí ẹ máa tẹ̀ lé, ì báà jẹ́ àjèjì tàbí ọmọ ìbílẹ̀.’”+
15 Ní ọjọ́ tí wọ́n to+ àgọ́ ìjọsìn, ìkùukùu* bo àgọ́ ìjọsìn náà, ìyẹn àgọ́ Ẹ̀rí, àmọ́ láti ìrọ̀lẹ́ títí di àárọ̀,+ ohun tó rí bí iná wà lórí àgọ́ ìjọsìn náà. 16 Bó ṣe máa ń ṣẹlẹ̀ nìyẹn: Ìkùukùu máa ń bò ó ní ọ̀sán, ohun tó rí bí iná sì máa ń bò ó ní òru.+ 17 Ìgbàkígbà tí ìkùukùu náà bá kúrò lórí àgọ́ náà, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì á gbéra+ kíákíá, ibi tí ìkùukùu náà bá sì dúró sí ni àwọn ọmọ Ísírẹ́lì máa pàgọ́+ sí. 18 Tí Jèhófà bá pàṣẹ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé kí wọ́n gbéra, wọ́n á gbéra, tí Jèhófà bá sì pàṣẹ pé kí wọ́n pàgọ́, wọ́n á pàgọ́.+ Wọn kì í tú àgọ́ wọn ká ní gbogbo ìgbà tí ìkùukùu náà bá fi wà lórí àgọ́ ìjọsìn. 19 Tí ìkùukùu náà bá wà lórí àgọ́ ìjọsìn fún ọ̀pọ̀ ọjọ́, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì máa ń ṣègbọràn sí Jèhófà, wọn ò sì ní tú àgọ́ wọn ká.+ 20 Nígbà míì, ìkùukùu máa ń wà lórí àgọ́ ìjọsìn fún ọjọ́ mélòó kan. Tí Jèhófà bá pàṣẹ pé kí wọ́n ṣì wà níbi tí wọ́n pàgọ́ sí, wọ́n á ṣe bẹ́ẹ̀, tí Jèhófà bá sì pàṣẹ pé kí wọ́n gbéra, wọ́n á gbéra. 21 Nígbà míì, ó lè má ju ìrọ̀lẹ́ sí àárọ̀ tí ìkùukùu náà á fi dúró, tí ìkùukùu náà bá sì gbéra ní àárọ̀, àwọn èèyàn náà máa gbéra. Ì báà jẹ́ ọ̀sán tàbí òru ni ìkùukùu náà gbéra, àwọn èèyàn náà máa gbéra.+ 22 Ì báà jẹ́ ọjọ́ méjì, oṣù kan tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ ni ìkùukùu náà fi wà lórí àgọ́ ìjọsìn, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ò ní tú àgọ́ wọn ká, wọn ò sì ní gbéra. Àmọ́ tó bá ti gbéra, àwọn náà á gbéra. 23 Tí Jèhófà bá pàṣẹ pé kí wọ́n pàgọ́, wọ́n á pàgọ́. Tí Jèhófà bá sì pàṣẹ pé kí wọ́n gbéra, wọ́n á gbéra. Wọ́n ń ṣe ojúṣe wọn sí Jèhófà bí Jèhófà ṣe pa á láṣẹ nípasẹ̀ Mósè.
10 Jèhófà wá sọ fún Mósè pé: 2 “Ṣe kàkàkí+ méjì fún ara rẹ, fàdákà tí wọ́n fi òòlù lù ni kí o fi ṣe é. Kí o máa fi pe àwọn èèyàn náà jọ pọ̀, kí o sì máa fi sọ fún wọn pé kí wọ́n tú àgọ́ wọn ká. 3 Tí wọ́n bá fun kàkàkí méjèèjì, kí gbogbo àpéjọ náà wá sọ́dọ̀ rẹ ní ẹnu ọ̀nà àgọ́ ìpàdé.+ 4 Tó bá jẹ́ pé kàkàkí kan ni wọ́n fun, àwọn ìjòyè, àwọn olórí ẹgbẹẹgbẹ̀rún ní Ísírẹ́lì nìkan ni kó pé jọ sọ́dọ̀ rẹ.+
5 “Tí ẹ bá fi kàkàkí náà fun ìró tó ń lọ sókè sódò, kí àwọn tó pàgọ́ sí apá ìlà oòrùn+ gbéra. 6 Tí ẹ bá fi kàkàkí náà fun ìró tó ń lọ sókè sódò lẹ́ẹ̀kejì, kí àwọn tó pàgọ́ sí apá gúúsù+ gbéra. Bí wọ́n á ṣe máa fun kàkàkí náà nìyí ní gbogbo ìgbà tí àwùjọ kọ̀ọ̀kan bá fẹ́ gbéra.
7 “Tí ẹ bá fẹ́ pe àwọn èèyàn náà jọ, kí ẹ fun àwọn kàkàkí+ náà, àmọ́ kí ẹ má ṣe jẹ́ kí ìró rẹ̀ lọ sókè sódò. 8 Àwọn ọmọ Áárónì, àwọn àlùfáà, ni kó máa fun àwọn kàkàkí+ náà. Kí ẹ máa lò ó, kó jẹ́ àṣẹ tó máa wà títí lọ fún yín jálẹ̀ àwọn ìran yín.
9 “Tí ẹ bá lọ bá ọ̀tá tó ń ni yín lára jagun ní ilẹ̀ yín, ẹ fi àwọn kàkàkí+ náà kéde ogun, Jèhófà Ọlọ́run yín yóò sì rántí yín, yóò gbà yín lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá yín.
10 “Bákan náà, ní àwọn ọjọ́ ayọ̀+ yín, ìyẹn, nígbà àwọn àjọyọ̀+ yín àti ní ìbẹ̀rẹ̀ àwọn oṣù yín, kí ẹ fun àwọn kàkàkí náà sórí àwọn ẹbọ sísun+ àti àwọn ẹbọ ìrẹ́pọ̀+ yín; wọ́n máa jẹ́ ohun ìrántí fún yín níwájú Ọlọ́run yín. Èmi ni Jèhófà Ọlọ́run+ yín.”
11 Ó ṣẹlẹ̀ pé ní ogúnjọ́ oṣù kejì, ọdún kejì,+ ìkùukùu* náà gbéra lórí àgọ́+ Ẹ̀rí. 12 Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì bẹ̀rẹ̀ sí í kúrò ní aginjù Sínáì, wọ́n tẹ̀ lé ètò tó wà nílẹ̀ nípa bí wọ́n ṣe máa gbéra,+ ìkùukùu náà sì dúró ní aginjù Páránì.+ 13 Èyí ni ìgbà àkọ́kọ́ tí wọ́n gbéra bí Jèhófà ṣe pa á láṣẹ nípasẹ̀ Mósè.+
14 Ẹ̀yà mẹ́ta ti ibùdó àwọn ọmọ Júdà ló kọ́kọ́ gbéra ní àwùjọ-àwùjọ,* Náṣónì+ ọmọ Ámínádábù sì ni olórí àwùjọ náà. 15 Nétánélì+ ọmọ Súárì ni olórí àwùjọ ẹ̀yà àwọn ọmọ Ísákà. 16 Élíábù+ ọmọ Hélónì ni olórí àwùjọ ẹ̀yà àwọn ọmọ Sébúlúnì.
17 Nígbà tí wọ́n tú àgọ́ ìjọsìn palẹ̀,+ àwọn ọmọ Gẹ́ṣónì+ àti àwọn ọmọ Mérárì+ tí wọ́n ru àgọ́ ìjọsìn náà gbéra.
18 Ẹ̀yà mẹ́ta ti ibùdó Rúbẹ́nì wá gbéra ní àwùjọ-àwùjọ,* Élísúrì+ ọmọ Ṣédéúrì sì ni olórí àwùjọ náà. 19 Ṣẹ́lúmíẹ́lì+ ọmọ Súríṣádáì ni olórí àwùjọ ẹ̀yà àwọn ọmọ Síméónì. 20 Élíásáfù+ ọmọ Déúélì ni olórí àwùjọ ẹ̀yà àwọn ọmọ Gádì.
21 Àwọn ọmọ Kóhátì tí wọ́n ru àwọn ohun èlò+ ibi mímọ́ wá gbéra. Wọ́n á ti to àgọ́ ìjọsìn náà tán kí wọ́n tó dé.
22 Ẹ̀yà mẹ́ta ti ibùdó àwọn ọmọ Éfúrémù náà gbéra ní àwùjọ-àwùjọ,* Élíṣámà+ ọmọ Ámíhúdù sì ni olórí àwùjọ náà. 23 Gàmálíẹ́lì+ ọmọ Pédásúrì ni olórí àwùjọ ẹ̀yà àwọn ọmọ Mánásè. 24 Ábídánì+ ọmọ Gídéónì sì ni olórí àwùjọ ẹ̀yà àwọn ọmọ Bẹ́ńjámínì.
25 Ẹ̀yà mẹ́ta ti ibùdó àwọn ọmọ Dánì wá gbéra ní àwùjọ-àwùjọ,* àwọn ni wọ́n wà lẹ́yìn tí wọ́n ń ṣọ́ gbogbo ibùdó náà. Áhíésérì+ ọmọ Ámíṣádáì ni olórí àwùjọ náà. 26 Págíẹ́lì+ ọmọ Ókíránì ni olórí àwùjọ ẹ̀yà àwọn ọmọ Áṣérì. 27 Áhírà+ ọmọ Énánì ni olórí àwùjọ ẹ̀yà àwọn ọmọ Náfútálì. 28 Bí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì àti àwọn àwùjọ wọn* ṣe máa ń tò tẹ̀ léra nìyí tí wọ́n bá fẹ́ gbéra.+
29 Mósè sọ fún Hóbábù ọmọ Réúẹ́lì*+ ọmọ ilẹ̀ Mídíánì, bàbá ìyàwó Mósè pé: “À ń lọ síbi tí Jèhófà sọ nípa rẹ̀ pé, ‘Èmi yóò fún yín.’+ Bá wa lọ,+ a ó sì tọ́jú rẹ dáadáa, torí Jèhófà ti ṣèlérí àwọn ohun rere fún Ísírẹ́lì.”+ 30 Àmọ́ ó fèsì pé: “Mi ò ní bá yín lọ. Mo máa pa dà sí ilẹ̀ mi àti sọ́dọ̀ àwọn mọ̀lẹ́bí mi.” 31 Ni Mósè bá sọ fún un pé: “Jọ̀ọ́, má fi wá sílẹ̀, torí o mọ ibi tí a lè pàgọ́ sí nínú aginjù, o sì lè fọ̀nà hàn wá.* 32 Tí o bá sì bá wa lọ,+ ó dájú pé ohun rere èyíkéyìí tí Jèhófà bá ṣe fún wa la máa ṣe fún ọ.”
33 Lẹ́yìn náà, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í kúrò ní òkè Jèhófà,+ wọ́n rin ìrìn ọjọ́ mẹ́ta, àpótí+ májẹ̀mú Jèhófà sì ń lọ níwájú wọn ní ọjọ́ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta láti wá ibi ìsinmi fún wọn.+ 34 Ìkùukùu+ Jèhófà sì wà lórí wọn ní ọ̀sán nígbà tí wọ́n gbéra ní ibùdó.
35 Nígbàkigbà tí wọ́n bá gbé Àpótí náà, Mósè á sọ pé: “Dìde, Jèhófà,+ jẹ́ kí àwọn ọ̀tá rẹ tú ká, kí àwọn tó kórìíra rẹ sì sá kúrò níwájú rẹ.” 36 Nígbà tí wọ́n bá sì gbé e kalẹ̀, á sọ pé: “Jèhófà, pa dà sọ́dọ̀ àìmọye ẹgbẹẹgbẹ̀rún* Ísírẹ́lì.”+
11 Àwọn èèyàn náà bá bẹ̀rẹ̀ sí í ráhùn gidigidi níwájú Jèhófà. Nígbà tí Jèhófà gbọ́, inú bí i gan-an, iná sì wá látọ̀dọ̀ Jèhófà, ó jó àwọn kan tó wà ní ìkángun ibùdó náà run. 2 Nígbà tí àwọn èèyàn náà bẹ̀rẹ̀ sí í ké pe Mósè, ó rawọ́ ẹ̀bẹ̀ sí Jèhófà,+ iná náà sì kú. 3 Wọ́n wá pe orúkọ ibẹ̀ ní Tábérà,* torí pé iná látọ̀dọ̀ Jèhófà jó wọn.+
4 Onírúurú èèyàn*+ tó wà láàárín wọn bá bẹ̀rẹ̀ sí í fi ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ọkàn+ wọn hàn, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì náà tún wá ń sunkún, wọ́n sì ń sọ pé: “Ta ló máa fún wa ní ẹran jẹ?+ 5 A ò jẹ́ gbàgbé ẹja tí a máa ń jẹ lọ́fẹ̀ẹ́ nílẹ̀ Íjíbítì àti kùkúńbà,* bàrà olómi, ewébẹ̀ líìkì, àlùbọ́sà àti ááyù!+ 6 Àmọ́ ní báyìí, a* ti ń kú lọ. A ò rí nǹkan míì jẹ yàtọ̀ sí mánà+ yìí.”
7 Ó ṣẹlẹ̀ pé mánà+ náà dà bí irúgbìn kọriáńdà,+ ó sì rí bíi gọ́ọ̀mù bídẹ́líọ́mù. 8 Àwọn èèyàn náà máa ń lọ káàkiri láti kó o, wọ́n á sì fi ọlọ lọ̀ ọ́ tàbí kí wọ́n gún un nínú odó. Wọ́n á wá sè é nínú ìkòkò tàbí kí wọ́n fi ṣe búrẹ́dì ribiti,+ bí àkàrà dídùn tí wọ́n fi òróró sí ló rí lẹ́nu. 9 Tí ìrì bá sẹ̀ sí ibùdó náà ní òru, mánà náà máa ń já bọ́ sórí rẹ̀.+
10 Mósè gbọ́ bí àwọn èèyàn náà ṣe ń sunkún, ní ìdílé kọ̀ọ̀kan, kálukú wà lẹ́nu ọ̀nà àgọ́ rẹ̀. Inú bí Jèhófà gan-an,+ inú Mósè náà ò sì dùn rárá. 11 Mósè wá sọ fún Jèhófà pé: “Kí ló dé tí o fìyà jẹ ìránṣẹ́ rẹ? Kí ló dé tí o kò ṣojúure sí mi, tí o sì di ẹrù gbogbo àwọn èèyàn yìí lé mi lórí?+ 12 Ṣé èmi ni mo lóyún gbogbo àwọn èèyàn yìí ni? Àbí èmi ni mo bí wọn, tí o fi ń sọ fún mi pé, ‘Gbé wọn sí àyà rẹ bí olùtọ́jú* ṣe máa ń gbé ọmọ tó ṣì ń mu ọmú’ lọ sí ilẹ̀ tí o búra pé o máa fún àwọn baba ńlá+ wọn? 13 Ibo ni kí n ti rí ẹran tí màá fún gbogbo àwọn èèyàn yìí? Torí wọ́n ń sunkún sí mi lọ́rùn, wọ́n ń sọ pé, ‘Fún wa ní ẹran jẹ!’ 14 Èmi nìkan ò lè gbé ẹrù gbogbo àwọn èèyàn yìí, ó ti wúwo jù fún mi.+ 15 Tó bá jẹ́ ohun tí o fẹ́ ṣe fún mi nìyí, jọ̀ọ́ kúkú pa mí báyìí.+ Tí mo bá rí ojúure rẹ, má ṣe jẹ́ kí ojú mi tún rí ibi mọ́.”
16 Jèhófà wá dá Mósè lóhùn pé: “Kó àádọ́rin (70) ọkùnrin jọ fún mi nínú àwọn àgbààgbà Ísírẹ́lì, àwọn tí o mọ̀ pé wọ́n jẹ́* àgbààgbà àti olórí láàárín àwọn èèyàn náà,+ kí o mú wọn lọ sí àgọ́ ìpàdé, kí wọ́n sì dúró níbẹ̀ pẹ̀lú rẹ. 17 Èmi yóò sọ̀ kalẹ̀+ wá bá ọ sọ̀rọ̀ níbẹ̀,+ mo máa mú lára ẹ̀mí+ tó wà lára rẹ, màá sì fi sára wọn, wọ́n á sì máa ràn ọ́ lọ́wọ́ láti ru ẹrù àwọn èèyàn náà, kí o má bàa dá ru ẹrù náà.+ 18 Kí o sọ fún àwọn èèyàn náà pé, ‘Ẹ sọ ara yín di mímọ́ de ọ̀la,+ ó dájú pé ẹ máa jẹ ẹran, torí Jèhófà ti gbọ́+ ẹkún tí ẹ̀ ń sun pé: “Ta ló máa fún wa ní ẹran jẹ? Nǹkan sàn ju báyìí lọ fún wa ní Íjíbítì.”+ Ó dájú pé Jèhófà máa fún yín ní ẹran, ẹ ó sì jẹ ẹ́.+ 19 Ẹ máa jẹ ẹ́, kì í ṣe ọjọ́ kan tàbí méjì lẹ máa fi jẹ ẹ́, bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe ọjọ́ márùn-ún tàbí mẹ́wàá tàbí ogún (20) ọjọ́ lẹ máa fi jẹ ẹ́, 20 àmọ́ oṣù kan gbáko ni, títí á fi jáde ní ihò imú yín, tó sì máa kó yín nírìíra,+ torí pé ẹ ti kọ Jèhófà, ẹni tó wà ní àárín yín, ẹ sì wá ń sunkún níwájú rẹ̀ pé: “Kí ló dé tí a kúrò ní Íjíbítì?”’”+
21 Mósè wá sọ pé: “Ọgbọ̀n ọ̀kẹ́ (600,000) ọkùnrin*+ la jọ wà níbí, síbẹ̀ ìwọ fúnra rẹ sọ pé, ‘Èmi yóò fún wọn ní ẹran, wọ́n á sì jẹ ẹ́ ni àjẹyó fún oṣù kan gbáko’! 22 Tí wọ́n bá pa gbogbo agbo ẹran àti ọ̀wọ́ ẹran, ṣé ó lè tó wọn? Tí wọ́n bá sì mú gbogbo ẹja inú òkun, ṣé ó máa tó wọn?”
23 Ni Jèhófà bá sọ fún Mósè pé: “Ṣé ọwọ́ Jèhófà kúrú+ ni? Ó máa ṣojú rẹ báyìí, bóyá ohun tí mo sọ máa ṣẹlẹ̀ sí ọ tàbí kò ní ṣẹlẹ̀.”
24 Mósè wá jáde lọ sọ ọ̀rọ̀ Jèhófà fún àwọn èèyàn náà. Ó sì kó àádọ́rin (70) ọkùnrin jọ lára àwọn àgbààgbà nínú àwọn èèyàn náà, ó sì mú wọn dúró yí àgọ́+ ká. 25 Jèhófà bá sọ̀ kalẹ̀ nínú ìkùukùu,*+ ó bá a+ sọ̀rọ̀, ó sì mú díẹ̀ lára ẹ̀mí+ tó wà lára rẹ̀, ó fi sára àwọn àádọ́rin (70) àgbààgbà náà lọ́kọ̀ọ̀kan. Gbàrà tí ẹ̀mí náà bà lé wọn, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe bíi wòlíì,*+ àmọ́ wọn ò tún ṣe bẹ́ẹ̀ mọ́.
26 Méjì lára àwọn ọkùnrin náà ṣì wà nínú ibùdó. Orúkọ wọn ni Ẹ́lídádì àti Médádì. Ẹ̀mí náà bà lé wọn torí wọ́n wà lára àwọn tí wọ́n kọ orúkọ wọn sílẹ̀, àmọ́ wọn ò lọ sí àgọ́. Wọ́n wá bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe bíi wòlíì nínú ibùdó. 27 Ọ̀dọ́kùnrin kan wá sáré lọ sọ fún Mósè pé: “Ẹ́lídádì àti Médádì ń ṣe bíi wòlíì nínú ibùdó!” 28 Jóṣúà+ ọmọ Núnì tó jẹ́ ìránṣẹ́ Mósè láti kékeré fèsì pé: “Mósè olúwa mi, pa wọ́n lẹ́nu mọ́!”+ 29 Àmọ́ Mósè dá a lóhùn pé: “Ṣé ò ń jowú torí mi ni? Má ṣe bẹ́ẹ̀, ó wù mí kí gbogbo èèyàn Jèhófà jẹ́ wòlíì, kí Jèhófà sì fi ẹ̀mí rẹ̀ sára wọn!” 30 Lẹ́yìn náà, Mósè àti àwọn àgbààgbà Ísírẹ́lì pa dà sí ibùdó.
31 Jèhófà wá mú kí afẹ́fẹ́ kan fẹ́ wá lójijì, ó gbá àwọn ẹyẹ àparò wá láti òkun, ó sì mú kí wọ́n já bọ́ yí ibùdó+ náà ká, nǹkan bí ìrìn àjò ọjọ́ kan lápá ibí àti ìrìn àjò ọjọ́ kan lápá ọ̀hún, yí ibùdó náà ká, ìpele wọn sì ga tó nǹkan bí ìgbọ̀nwọ́* méjì sílẹ̀. 32 Tọ̀sántòru ọjọ́ yẹn àti gbogbo ọjọ́ kejì ni àwọn èèyàn náà ò fi sùn, tí wọ́n ń kó àparò. Kò sẹ́ni tó kó iye tó dín sí òṣùwọ̀n hómérì* mẹ́wàá, wọ́n sì ń sá a yí ibùdó náà ká. 33 Àmọ́ nígbà tí ẹran náà ṣì wà láàárín eyín wọn, kí wọ́n tó jẹ ẹ́ lẹ́nu, Jèhófà bínú sí àwọn èèyàn náà gidigidi, Jèhófà sì bẹ̀rẹ̀ sí í pa àwọn èèyàn náà lọ rẹpẹtẹ.+
34 Wọ́n wá pe ibẹ̀ ní Kiburoti-hátááfà,*+ torí ibẹ̀ ni wọ́n sin àwọn èèyàn tó hùwà wọ̀bìà torí ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ọkàn+ wọn sí. 35 Àwọn èèyàn náà kúrò ní Kiburoti-hátááfà lọ sí Hásérótì, wọ́n sì dúró sí Hásérótì.+
12 Míríámù àti Áárónì wá ń sọ̀rọ̀ tí kò dáa sí Mósè torí ọmọ ilẹ̀ Kúṣì tó fi ṣe aya, torí pé ó fẹ́ ọmọbìnrin ará Kúṣì.+ 2 Wọ́n ń sọ pé: “Ṣé ẹnu Mósè nìkan ni Jèhófà gbà sọ̀rọ̀ ni? Ṣé kò gbẹnu tiwa náà sọ̀rọ̀ ni?”+ Jèhófà sì ń fetí sílẹ̀.+ 3 Ọkùnrin náà, Mósè, ló jẹ́ oníwà pẹ̀lẹ́ jù lọ nínú gbogbo èèyàn*+ tó wà láyé.
4 Lójijì, Jèhófà sọ fún Mósè, Áárónì àti Míríámù pé: “Ẹ̀yin mẹ́tẹ̀ẹ̀ta, ẹ jáde lọ sí àgọ́ ìpàdé.” Àwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta sì lọ. 5 Jèhófà wá sọ̀ kalẹ̀ wá nínú ọwọ̀n ìkùukùu,*+ ó dúró ní ẹnu ọ̀nà àgọ́, ó sì pe Áárónì àti Míríámù. Àwọn méjèèjì sì bọ́ síwájú. 6 Ó wá sọ pé: “Ẹ jọ̀ọ́, ẹ tẹ́tí kí ẹ gbọ́ mi. Tí wòlíì Jèhófà bá wà láàárín yín, màá jẹ́ kó mọ̀ mí nínú ìran,+ màá sì bá a sọ̀rọ̀ lójú àlá.+ 7 Àmọ́ ọ̀rọ̀ ò rí bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú Mósè ìránṣẹ́ mi! Ìkáwọ́ rẹ̀ ni gbogbo ilé+ mi wà.* 8 Ojúkojú* ni mò ń bá a sọ̀rọ̀,+ láì fọ̀rọ̀ pa mọ́, kì í ṣe lówelówe; ìrísí Jèhófà ló sì ń rí. Kí wá nìdí tí ẹ̀rù ò fi bà yín láti sọ̀rọ̀ tí kò dáa sí Mósè ìránṣẹ́ mi?”
9 Jèhófà bínú sí wọn gidigidi, ó sì kúrò lọ́dọ̀ wọn. 10 Ìkùukùu wá kúrò lórí àgọ́ náà, wò ó! ẹ̀tẹ̀ tó funfun bíi yìnyín+ sì bo Míríámù. Ni Áárónì bá yíjú sọ́dọ̀ Míríámù, ó sì rí i pé ẹ̀tẹ̀+ ti bò ó. 11 Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, Áárónì sọ fún Mósè pé: “Mo bẹ̀ ọ́ olúwa mi! Jọ̀ọ́, má ka ẹ̀ṣẹ̀ yìí sí wa lọ́rùn! Ìwà òmùgọ̀ gbáà la hù yìí. 12 Jọ̀ọ́, má ṣe jẹ́ ká fi sílẹ̀ báyìí bí ẹni tó ti kú, tí ìdajì ara rẹ̀ ti jẹrà kí wọ́n tó bí i!” 13 Mósè wá bẹ̀rẹ̀ sí í ké pe Jèhófà, ó ní: “Ọlọ́run, jọ̀ọ́ mú un lára dá! Jọ̀ọ́!”+
14 Jèhófà dá Mósè lóhùn pé: “Tó bá jẹ́ bàbá rẹ̀ ló tutọ́ sí i lójú, ǹjẹ́ ọjọ́ méje kọ́ lojú fi máa tì í? Ẹ lọ sé e mọ́ ẹ̀yìn ibùdó+ fún ọjọ́ méje, lẹ́yìn náà, kí ẹ jẹ́ kó wọlé.” 15 Torí náà, wọ́n sé Míríámù mọ́ ẹ̀yìn ibùdó fún ọjọ́ méje,+ àwọn èèyàn náà ò sì tú àgọ́ wọn ká títí Míríámù fi pa dà wọlé. 16 Àwọn èèyàn náà wá kúrò ní Hásérótì,+ wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í pàgọ́ sí aginjù Páránì.+
13 Jèhófà wá sọ fún Mósè pé: 2 “Rán àwọn ọkùnrin lọ ṣe amí* ilẹ̀ Kénáánì tí mo fẹ́ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì. Kí ẹ rán ọkùnrin kan látinú ẹ̀yà baba ńlá wọn kọ̀ọ̀kan, kí ọ̀kọ̀ọ̀kan sì jẹ́ ìjòyè+ láàárín wọn.”+
3 Torí náà, Mósè rán wọn jáde láti aginjù Páránì+ bí Jèhófà ṣe pa á láṣẹ. Gbogbo àwọn ọkùnrin náà jẹ́ olórí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì. 4 Orúkọ wọn nìyí: Nínú ẹ̀yà Rúbẹ́nì, Ṣámúà ọmọ Sákúrì; 5 nínú ẹ̀yà Síméónì, Ṣáfátì ọmọ Hórì; 6 nínú ẹ̀yà Júdà, Kélẹ́bù+ ọmọ Jéfúnè; 7 nínú ẹ̀yà Ísákà, Ígálì ọmọ Jósẹ́fù; 8 nínú ẹ̀yà Éfúrémù, Hóṣéà+ ọmọ Núnì; 9 nínú ẹ̀yà Bẹ́ńjámínì, Pálítì ọmọ Ráfù; 10 nínú ẹ̀yà Sébúlúnì, Gádíélì ọmọ Sódì; 11 nínú ẹ̀yà Jósẹ́fù,+ fún ẹ̀yà Mánásè,+ Gádáì ọmọ Súsì; 12 nínú ẹ̀yà Dánì, Ámíélì ọmọ Gémálì; 13 nínú ẹ̀yà Áṣérì, Sẹ́túrì ọmọ Máíkẹ́lì; 14 nínú ẹ̀yà Náfútálì, Náhíbì ọmọ Fófísì; 15 nínú ẹ̀yà Gádì, Géúélì ọmọ Mákì. 16 Èyí ni orúkọ àwọn ọkùnrin tí Mósè rán láti ṣe amí ilẹ̀ náà. Mósè wá sọ Hóṣéà ọmọ Núnì ní Jóṣúà.*+
17 Nígbà tí Mósè ń rán wọn lọ ṣe amí ilẹ̀ Kénáánì, ó sọ fún wọn pé: “Ẹ gòkè lọ sí Négébù, kí ẹ sì lọ sí agbègbè olókè.+ 18 Kí ẹ lọ wo irú ilẹ̀ tó jẹ́,+ kí ẹ sì wò ó bóyá àwọn tó ń gbé ibẹ̀ lágbára tàbí wọn ò lágbára, bóyá wọ́n pọ̀ tàbí wọn ò pọ̀, 19 kí ẹ wò ó bóyá ilẹ̀ náà dáa tàbí kò dáa, bóyá inú àgọ́ làwọn èèyàn ilẹ̀ náà ń gbé àbí àwọn ìlú wọn ní ààbò. 20 Kí ẹ wádìí bóyá ilẹ̀ náà lọ́rọ̀* àbí kò lọ́rọ̀,*+ bóyá igi wà níbẹ̀ àbí kò sí. Ẹ jẹ́ onígboyà,+ kí ẹ sì mú lára èso ilẹ̀ náà bọ̀.” Ó ṣẹlẹ̀ pé àkókò yẹn ni àkọ́pọ́n èso àjàrà+ máa ń jáde.
21 Torí náà, wọ́n gòkè lọ, wọ́n sì ṣe amí ilẹ̀ náà láti aginjù Síínì+ dé Réhóbù+ ní tòsí Lebo-hámátì.*+ 22 Nígbà tí wọ́n gòkè lọ sí Négébù, wọ́n dé Hébúrónì.+ Ibẹ̀ ni Áhímánì, Ṣéṣáì àti Tálímáì,+ tí wọ́n jẹ́ Ánákímù+ ń gbé. Ó ṣẹlẹ̀ pé, ọdún méje ni wọ́n ti kọ́ Hébúrónì ṣáájú Sóánì ti ilẹ̀ Íjíbítì. 23 Nígbà tí wọ́n dé Àfonífojì Éṣíkólì,+ wọ́n gé ẹ̀ka àjàrà tó ní òṣùṣù èso àjàrà kan, méjì lára àwọn ọkùnrin náà sì fi ọ̀pá gbọọrọ kan gbé e, pẹ̀lú pómégíránétì díẹ̀ àti èso ọ̀pọ̀tọ́+ díẹ̀. 24 Wọ́n pe ibẹ̀ ní Àfonífojì Éṣíkólì,*+ torí òṣùṣù èso tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì gé níbẹ̀.
25 Lẹ́yìn ogójì (40) ọjọ́,+ wọ́n pa dà láti ilẹ̀ tí wọ́n ti lọ ṣe amí. 26 Wọ́n sì pa dà sọ́dọ̀ Mósè àti Áárónì àti gbogbo àpéjọ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní aginjù Páránì, ní Kádéṣì.+ Wọ́n jábọ̀ fún gbogbo àpéjọ náà, wọ́n sì fi àwọn èso ilẹ̀ náà hàn wọ́n. 27 Ohun tí wọ́n ròyìn fún Mósè ni pé: “A dé ilẹ̀ tí o rán wa lọ, wàrà àti oyin+ sì ń ṣàn níbẹ̀ lóòótọ́, àwọn èso+ ibẹ̀ nìyí. 28 Àmọ́, àwọn tó ń gbé ilẹ̀ náà lágbára, àwọn ìlú olódi náà sì tóbi gan-an. A tún rí àwọn Ánákímù níbẹ̀.+ 29 Àwọn ọmọ Ámálékì+ ń gbé ilẹ̀ Négébù,+ àwọn ọmọ Hétì, àwọn ará Jébúsì+ àti àwọn Ámórì+ ń gbé ní agbègbè olókè, àwọn ọmọ Kénáánì+ sì ń gbé létí òkun+ àti lẹ́gbẹ̀ẹ́ Jọ́dánì.”
30 Kélẹ́bù wá gbìyànjú láti fi àwọn èèyàn náà lọ́kàn balẹ̀ bí wọ́n ṣe dúró níwájú Mósè, ó sọ pé: “Ẹ jẹ́ ká gòkè lọ láìjáfara, ó dájú pé a máa gba ilẹ̀ náà, torí ó dájú pé a máa borí wọn.”+ 31 Àmọ́ àwọn ọkùnrin tí wọ́n jọ lọ sọ pé: “A ò lè lọ bá àwọn èèyàn náà jà, torí wọ́n lágbára jù wá lọ.”+ 32 Wọ́n sì ń ròyìn ohun tí kò dáa+ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nípa ilẹ̀ tí wọ́n lọ ṣe amí rẹ̀, wọ́n ní: “Ilẹ̀ tó ń jẹ àwọn tó ń gbé inú rẹ̀ run ni ilẹ̀ tí a lọ ṣe amí rẹ̀, gbogbo àwọn èèyàn tí a sì rí níbẹ̀ ló tóbi yàtọ̀.+ 33 A rí àwọn Néfílímù níbẹ̀, àwọn ọmọ Ánákì,+ tí wọ́n jẹ́ àtọmọdọ́mọ* àwọn Néfílímù. Lójú wọn, ṣe la dà bíi tata, bẹ́ẹ̀ náà ló sì rí lójú tiwa.”
14 Gbogbo àpéjọ náà ń kígbe, àwọn èèyàn náà ń ké, wọ́n sì ń sunkún ní gbogbo òru+ yẹn. 2 Gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì wá bẹ̀rẹ̀ sí í kùn sí Mósè àti Áárónì,+ gbogbo àpéjọ náà sì ń sọ̀rọ̀ tí kò dáa sí wọn pé: “Ó sàn ká ti kú sí ilẹ̀ Íjíbítì tàbí ká tiẹ̀ ti kú sínú aginjù yìí! 3 Kí ló dé tí Jèhófà fẹ́ mú wa wá sí ilẹ̀ yìí kí wọ́n lè fi idà+ pa wá? Wọ́n á kó+ àwọn ìyàwó wa àti àwọn ọmọ wa lẹ́rú. Ǹjẹ́ kò ní dáa ká pa dà sí Íjíbítì?”+ 4 Wọ́n tiẹ̀ ń sọ fún ara wọn pé: “Ẹ jẹ́ ká yan ẹnì kan ṣe olórí wa, ká sì pa dà sí Íjíbítì!”+
5 Mósè àti Áárónì wá wólẹ̀ lójú gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tí wọ́n pé jọ. 6 Jóṣúà+ ọmọ Núnì àti Kélẹ́bù+ ọmọ Jéfúnè, tí wọ́n wà lára àwọn tó lọ ṣe amí ilẹ̀ náà wá fa aṣọ wọn ya, 7 wọ́n sì sọ fún gbogbo àpéjọ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé: “Ilẹ̀ tí a lọ ṣe amí rẹ̀ dára gan-an ni.+ 8 Bí inú Jèhófà bá dùn sí wa, ó dájú pé ó máa mú wa dé ilẹ̀ yìí, ó sì máa fún wa, ilẹ̀ tí wàrà àti oyin ti ń ṣàn ni.+ 9 Àmọ́ ẹ má ṣọ̀tẹ̀ sí Jèhófà, ẹ má sì bẹ̀rù àwọn èèyàn ilẹ̀ náà,+ torí a máa jẹ wọ́n run.* Ààbò wọn ti kúrò lórí wọn, Jèhófà sì wà pẹ̀lú wa.+ Ẹ má bẹ̀rù wọn.”
10 Síbẹ̀, gbogbo àwọn èèyàn náà sọ pé àwọn máa sọ wọ́n lókùúta.+ Àmọ́ ògo Jèhófà fara han gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì+ lórí àgọ́ ìpàdé.
11 Jèhófà wá sọ fún Mósè pé: “Ìgbà wo ni àwọn èèyàn yìí máa jáwọ́ nínú fífojú di mí?+ Ìgbà wo sì ni wọ́n máa tó nígbàgbọ́ nínú mi pẹ̀lú gbogbo iṣẹ́ àmì tí mo ṣe láàárín wọn?+ 12 Jẹ́ kí n fi àjàkálẹ̀ àrùn kọ lù wọ́n, kí n sì lé wọn lọ, sì jẹ́ kí n sọ ìwọ di orílẹ̀-èdè ńlá, tó máa lágbára jù wọ́n lọ.”+
13 Àmọ́ Mósè sọ fún Jèhófà pé: “Àwọn ọmọ Íjíbítì tí o fi agbára rẹ mú àwọn èèyàn yìí kúrò láàárín wọn á gbọ́,+ 14 wọ́n á sì sọ fún àwọn tó ń gbé ilẹ̀ yìí. Àwọn náà ti gbọ́ pé ìwọ Jèhófà wà pẹ̀lú àwọn èèyàn+ yìí, o sì ti fara hàn wọ́n lójúkojú.+ Ìwọ ni Jèhófà, ìkùukùu rẹ sì wà lórí wọn, ò ń lọ níwájú wọn nínú ọwọ̀n ìkùukùu* ní ọ̀sán àti nínú ọwọ̀n iná* ní òru.+ 15 Tí o bá pa gbogbo àwọn èèyàn yìí lẹ́ẹ̀kan náà,* àwọn orílẹ̀-èdè tí òkìkí rẹ ti kàn dé ọ̀dọ̀ wọn máa sọ pé: 16 ‘Jèhófà ò lè mú àwọn èèyàn yìí dé ilẹ̀ tó búra pé òun máa fún wọn, ló bá pa wọ́n sí aginjù.’+ 17 Ní báyìí Jèhófà, jọ̀ọ́, fi agbára ńlá rẹ hàn, bí ìlérí tí o ṣe, pé: 18 ‘Jèhófà, Ọlọ́run tí kì í tètè bínú, tí ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀*+ sì pọ̀ gan-an, tó ń dárí ìṣìnà àti ẹ̀ṣẹ̀ jini, àmọ́ tí kò ní ṣàìfi ìyà jẹ ẹlẹ́ṣẹ̀, tó ń fi ìyà ẹ̀ṣẹ̀ àwọn bàbá jẹ àwọn ọmọ, dórí ìran kẹta àti dórí ìran kẹrin.’+ 19 Jọ̀ọ́, ro ti ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ tó pọ̀ gan-an, kí o sì dárí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn èèyàn yìí jì wọ́n, bí o ṣe ń dárí jì wọ́n láti Íjíbítì títí di báyìí.”+
20 Jèhófà wá sọ pé: “Mo dárí jì wọ́n bí o ṣe sọ.+ 21 Àmọ́ ṣá o, ó dájú pé bí mo ti wà láàyè, ògo Jèhófà+ máa kún gbogbo ayé. 22 Síbẹ̀, kò sí ìkankan nínú àwọn tó fojú rí ògo mi àti àwọn iṣẹ́ àmì+ mi tí mo ṣe ní Íjíbítì àti ní aginjù, tó tún wá ń dán mi wò+ nígbà mẹ́wàá yìí, tí kò sì fetí sí ohùn mi,+ 23 tó máa rí ilẹ̀ tí mo búra pé màá fún àwọn bàbá wọn. Àní, ìkankan nínú àwọn tó ń fojú di mí kò ní rí ilẹ̀ náà.+ 24 Àmọ́ torí pé ẹ̀mí tí Kélẹ́bù+ ìránṣẹ́ mi ní yàtọ̀, tó sì ń fi gbogbo ọkàn rẹ̀ tẹ̀ lé mi, ó dájú pé màá mú un wá sí ilẹ̀ tó lọ, yóò sì di ti+ àtọmọdọ́mọ rẹ̀. 25 Torí pé àfonífojì* ni àwọn ọmọ Ámálékì àti àwọn ọmọ Kénáánì+ ń gbé, kí ẹ ṣẹ́rí pa dà lọ́la, kí ẹ sì gba ọ̀nà Òkun Pupa+ lọ sínú aginjù.”
26 Jèhófà wá sọ fún Mósè àti Áárónì pé: 27 “Ìgbà wo ni àwọn èèyàn burúkú yìí máa tó jáwọ́ kíkùn sí mi?+ Mo ti gbọ́ ohun táwọn ọmọ Ísírẹ́lì ń sọ nígbà tí wọ́n ń kùn sí mi.+ 28 Sọ fún wọn pé, ‘“Ó dájú pé bí mo ti wà láàyè,” ni Jèhófà wí, “ohun tí mo gbọ́ tí ẹ sọ+ gẹ́lẹ́ ni màá ṣe sí yín! 29 Inú aginjù yìí lẹ máa kú sí,+ àní gbogbo àwọn tó jẹ́ ẹni ogún (20) ọdún sókè nínú yín, àwọn tí wọ́n forúkọ wọn sílẹ̀, gbogbo ẹ̀yin tí ẹ kùn sí mi.+ 30 Ìkankan nínú yín kò ní wọ ilẹ̀ tí mo búra* pé ẹ máa gbé,+ àfi Kélẹ́bù ọmọ Jéfúnè àti Jóṣúà ọmọ Núnì.+
31 “‘“Àwọn ọmọ yín tí ẹ sọ pé wọ́n máa kó+ lẹ́rú ni màá mú débẹ̀, wọ́n á sì mọ ilẹ̀ tí ẹ kọ̀+ náà. 32 Àmọ́ inú aginjù yìí ni ẹ̀yin máa kú sí. 33 Ogójì (40) ọdún+ ni àwọn ọmọ yín fi máa ṣe olùṣọ́ àgùntàn nínú aginjù, wọ́n sì máa jìyà ìwà àìṣòótọ́ tí ẹ hù* títí ẹni tó kẹ́yìn nínú yín fi máa kú sínú aginjù.+ 34 Ogójì (40) ọjọ́+ lẹ fi ṣe amí ilẹ̀ náà, àmọ́ ogójì (40) ọdún+ lẹ máa fi jìyà ẹ̀ṣẹ̀ yín, ọjọ́ kan fún ọdún kan, ọjọ́ kan fún ọdún kan, ẹ ó wá mọ ohun tó túmọ̀ sí láti ta kò mí.*
35 “‘“Èmi Jèhófà ti sọ̀rọ̀. Ohun tí màá ṣe fún àwọn èèyàn burúkú yìí tí wọ́n kóra jọ láti ta kò mí nìyí: Inú aginjù yìí ni wọ́n máa ṣègbé sí, ibí ni wọ́n sì máa kú sí.+ 36 Àwọn ọkùnrin tí Mósè rán lọ ṣe amí ilẹ̀ náà, tí wọ́n mú ìròyìn burúkú wá nípa ilẹ̀ náà,+ tí wọ́n sì wá mú kí gbogbo àpéjọ náà máa kùn sí i, 37 àní, Jèhófà+ máa kọ lu àwọn ọkùnrin tó mú ìròyìn burúkú wá nípa ilẹ̀ náà, wọ́n á sì kú níwájú rẹ̀. 38 Àmọ́ ó dájú pé Jóṣúà ọmọ Núnì àti Kélẹ́bù ọmọ Jéfúnè, tí wọ́n wà lára àwọn ọkùnrin tó lọ ṣe amí ilẹ̀ náà máa wà láàyè.”’”+
39 Nígbà tí Mósè sọ àwọn ọ̀rọ̀ yìí fún gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, àwọn èèyàn náà bẹ̀rẹ̀ sí í ṣọ̀fọ̀ gidigidi. 40 Síbẹ̀, wọ́n dìde ní àárọ̀ kùtù, wọ́n sì gbìyànjú láti lọ sórí òkè náà, wọ́n sọ pé: “A ti ṣe tán láti lọ síbi tí Jèhófà sọ, torí a ti ṣẹ̀.”+ 41 Àmọ́ Mósè sọ pé: “Kí ló dé tí ẹ̀ ń ṣe kọjá ohun tí Jèhófà pa láṣẹ? Ohun tí ẹ fẹ́ ṣe yìí kò ní yọrí sí rere. 42 Ẹ má gòkè lọ, torí Jèhófà ò sí pẹ̀lú yín; ṣe ni àwọn ọ̀tá+ yín máa ṣẹ́gun yín. 43 Àwọn ọmọ Ámálékì àti àwọn ọmọ Kénáánì máa bá yín jà,+ wọ́n á sì fi idà ṣẹ́gun yín. Torí pé ẹ ti fi Jèhófà sílẹ̀, Jèhófà ò ní tì yín lẹ́yìn.”+
44 Síbẹ̀, wọ́n ṣorí kunkun,* wọ́n sì lọ sí orí òkè+ náà, àmọ́ àpótí májẹ̀mú Jèhófà àti Mósè kò kúrò ní àárín ibùdó.+ 45 Àwọn ọmọ Ámálékì àti àwọn ọmọ Kénáánì tí wọ́n ń gbé ní òkè yẹn wá sọ̀ kalẹ̀, wọ́n bá wọn jà, wọ́n sì ń tú wọn ká títí lọ dé Hóómà.+
15 Jèhófà ń bá ọ̀rọ̀ tó ń sọ fún Mósè lọ pé: 2 “Sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé, ‘Tí ẹ bá dé ilẹ̀ tí màá fún yín pé kí ẹ máa gbé+ 3 tí ẹ sì mú nínú ọ̀wọ́ ẹran tàbí agbo ẹran láti fi ṣe ọrẹ àfinásun sí Jèhófà, ì bàá jẹ́ ẹbọ sísun+ tàbí ẹbọ tí ẹ rú láti san ẹ̀jẹ́ pàtàkì tàbí ọrẹ àtinúwá+ tàbí ọrẹ tí ẹ mú wá nígbà àwọn àjọyọ̀ àtìgbàdégbà+ yín láti mú òórùn dídùn* jáde sí Jèhófà,+ 4 kí ẹni tó ń mú ọrẹ rẹ̀ wá fún Jèhófà tún mú ọrẹ ọkà wá, kó jẹ́ ìyẹ̀fun tó kúnná+ tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ ìdá mẹ́wàá òṣùwọ̀n eéfà,* tó pò mọ́ òróró ìlàrin òṣùwọ̀n hínì.* 5 Kí o tún fi wáìnì ṣe ọrẹ ohun mímu, kó jẹ́ ìlàrin òṣùwọ̀n hínì pẹ̀lú ẹbọ sísun+ náà tàbí pẹ̀lú ẹbọ kọ̀ọ̀kan tí ẹ fi akọ ọ̀dọ́ àgùntàn ṣe. 6 Tó bá jẹ́ àgbò lo fẹ́ fi rúbọ, kí o mú ọrẹ ọkà wá, kí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ ìdá méjì nínú mẹ́wàá ìyẹ̀fun tó kúnná, tí o pò mọ́ òróró ìdá mẹ́ta òṣùwọ̀n hínì. 7 Kí o sì mú wáìnì wá láti ṣe ọrẹ ohun mímu, kó jẹ́ ìdá mẹ́ta òṣùwọ̀n hínì, láti mú òórùn dídùn* jáde sí Jèhófà.
8 “‘Àmọ́ tó bá jẹ́ akọ lo mú wá látinú ọ̀wọ́ ẹran láti fi rú ẹbọ sísun+ tàbí ẹbọ láti fi san ẹ̀jẹ́ pàtàkì+ tàbí láti fi rú àwọn ẹbọ ìrẹ́pọ̀ fún Jèhófà,+ 9 kí o tún mú ọrẹ ọkà+ wá pẹ̀lú akọ ẹran tí o mú wá látinú ọ̀wọ́ ẹran. Kí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ ìdá mẹ́ta nínú mẹ́wàá òṣùwọ̀n eéfà, kó jẹ́ ìyẹ̀fun tó kúnná tí o pò mọ́ òróró ìdajì òṣùwọ̀n hínì. 10 Kí o tún mú wáìnì wá láti fi ṣe ọrẹ ohun mímu,+ kó jẹ́ ìdajì òṣùwọ̀n hínì, kí o fi ṣe ọrẹ àfinásun tó ní òórùn dídùn* sí Jèhófà. 11 Ohun tí ẹ máa ṣe fún akọ màlúù kọ̀ọ̀kan nìyí tàbí àgbò kọ̀ọ̀kan tàbí ọ̀kọ̀ọ̀kan nínú àwọn akọ ọ̀dọ́ àgùntàn tàbí àwọn ewúrẹ́. 12 Kí ẹ ṣe bẹ́ẹ̀ fún ọ̀kọ̀ọ̀kan, bí wọ́n bá ṣe pọ̀ tó, iyekíye tí ẹ bá mú wá. 13 Bí ẹnì kọ̀ọ̀kan tó jẹ́ ọmọ bíbí Ísírẹ́lì á ṣe máa mú ọrẹ àfinásun wá nìyí, láti mú òórùn dídùn* jáde sí Jèhófà.
14 “‘Tí àjèjì kan tí ẹ jọ ń gbé tàbí ẹni tó ti wà láàárín yín láti ìrandíran pẹ̀lú bá fẹ́ ṣe ọrẹ àfinásun, láti mú òórùn dídùn* jáde sí Jèhófà, ohun tí ẹ ṣe gẹ́lẹ́ ni kó ṣe.+ 15 Àṣẹ kan náà ni kí ìjọ yín àti àjèjì tí ẹ jọ ń gbé máa tẹ̀ lé. Yóò jẹ́ àṣẹ tó máa wà títí lọ, jálẹ̀ àwọn ìran yín. Bákan náà ni kí ẹ̀yin àti àjèjì rí níwájú Jèhófà.+ 16 Òfin kan náà àti ìdájọ́ kan náà ni kí ẹ̀yin àti àjèjì tí ẹ jọ ń gbé máa tẹ̀ lé.’”
17 Jèhófà ń bá ọ̀rọ̀ tó ń sọ fún Mósè lọ pé: 18 “Sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé, ‘Tí ẹ bá dé ilẹ̀ tí mò ń mú yín lọ, 19 tí ẹ sì jẹ èyíkéyìí nínú oúnjẹ* ilẹ̀ náà,+ kí ẹ mú ọrẹ wá fún Jèhófà. 20 Kí ẹ mú ọrẹ wá látinú àkọ́so+ ọkà yín tí ẹ kò lọ̀ kúnná, kí ẹ fi ṣe àwọn búrẹ́dì tó rí bí òrùka. Bí ọrẹ ibi ìpakà ni kí ẹ ṣe mú un wá. 21 Kí ẹ máa fi lára àkọ́so ọkà yín tí ẹ kò lọ̀ kúnná ṣe ọrẹ fún Jèhófà jálẹ̀ àwọn ìran yín.
22 “‘Bó bá wá ṣẹlẹ̀ pé ẹ ṣe àṣìṣe, tí ẹ ò sì pa gbogbo àṣẹ yìí tí Jèhófà sọ fún Mósè mọ́, 23 gbogbo ohun tí Jèhófà pa láṣẹ fún yín nípasẹ̀ Mósè láti ọjọ́ tí Jèhófà ti pàṣẹ àti jálẹ̀ àwọn ìran yín, 24 tó sì jẹ́ pé àṣìṣe ni, tí gbogbo àpéjọ náà ò sì mọ̀, kí gbogbo àpéjọ náà mú akọ ọmọ màlúù kan wá láti fi rú ẹbọ sísun tó máa mú òórùn dídùn* jáde sí Jèhófà, pẹ̀lú ọrẹ ọkà rẹ̀ àti ọrẹ ohun mímu rẹ̀ bí ẹ ṣe máa ń ṣe é,+ pẹ̀lú ọmọ ewúrẹ́ kan láti fi rú ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀.+ 25 Kí àlùfáà ṣe ètùtù fún gbogbo àpéjọ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, wọ́n á sì rí ìdáríjì,+ torí pé àṣìṣe ni, wọ́n ti mú ọrẹ àfinásun wá fún Jèhófà, wọ́n sì ti mú ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ wọn wá síwájú Jèhófà nítorí àṣìṣe wọn. 26 Gbogbo àpéjọ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì àti àjèjì tí wọ́n jọ ń gbé máa rí ìdáríjì, torí pé àṣìṣe ni gbogbo àwọn èèyàn náà ṣe.
27 “‘Tí ẹnikẹ́ni* bá ṣèèṣì dẹ́ṣẹ̀, kó mú abo ewúrẹ́ ọlọ́dún kan wá láti fi rú ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀.+ 28 Kí àlùfáà sì ṣe ètùtù fún ẹni* tó ṣe àṣìṣe náà, tó ṣẹ̀ láìmọ̀ọ́mọ̀ níwájú Jèhófà, kó lè ṣe ètùtù fún un, ó sì máa rí ìdáríjì.+ 29 Òfin kan náà ni kí ọmọ ìbílẹ̀ Ísírẹ́lì àti àjèjì tí wọ́n jọ ń gbé máa tẹ̀ lé tí ẹnì kan bá ṣe ohun kan láìmọ̀ọ́mọ̀.+
30 “‘Ṣùgbọ́n ẹni* tó bá mọ̀ọ́mọ̀ ṣe+ ohun kan ń kó ẹ̀gàn bá Jèhófà, ì báà jẹ́ ọmọ ìbílẹ̀ tàbí àjèjì, torí náà, ṣe ni kí ẹ pa á, kí ẹ lè mú un kúrò láàárín àwọn èèyàn rẹ̀. 31 Torí pé ó ti tàbùkù sí ọ̀rọ̀ Jèhófà, kò sì pa àṣẹ rẹ̀ mọ́, ẹ gbọ́dọ̀ pa+ ẹni* náà. Ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ wà lọ́rùn rẹ̀.’”+
32 Nígbà tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì wà ní aginjù, wọ́n rí ọkùnrin kan tó ń ṣa igi ní ọjọ́ Sábáàtì.+ 33 Àwọn tó rí i níbi tó ti ń ṣa igi wá mú un lọ sọ́dọ̀ Mósè àti Áárónì àti gbogbo àpéjọ náà. 34 Wọ́n sì fi sínú àhámọ́,+ torí òfin ò tíì sọ ohun tí wọ́n máa ṣe fún un.
35 Jèhófà wá sọ fún Mósè pé: “Ẹ gbọ́dọ̀ pa+ ọkùnrin náà, kí gbogbo àpéjọ sọ ọ́ ní òkúta ní ẹ̀yìn ibùdó.”+ 36 Torí náà, gbogbo àpéjọ náà mú un lọ sí ẹ̀yìn ibùdó, wọ́n sì sọ ọ́ ní òkúta pa, bí Jèhófà ṣe pa á láṣẹ fún Mósè.
37 Jèhófà wá sọ ọ̀rọ̀ yìí fún Mósè pé: 38 “Sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé wọ́n gbọ́dọ̀ máa ṣe wajawaja sí etí aṣọ wọn nísàlẹ̀ jálẹ̀ àwọn ìran wọn, kí wọ́n sì máa fi okùn tín-ín-rín aláwọ̀ búlúù sókè wajawaja tó wà nísàlẹ̀ aṣọ+ wọn. 39 ‘Kí ẹ máa ṣe wajawaja náà síbẹ̀, kí ẹ lè máa rí i, kó sì máa rán yín létí gbogbo àṣẹ Jèhófà, kí ẹ sì máa pa wọ́n mọ́.+ Ẹ ò gbọ́dọ̀ tẹ̀ lé ọkàn àti ojú yín tó ń mú kí ẹ lọ ṣe àgbèrè ẹ̀sìn.+ 40 Èyí á máa rán yín létí, ẹ ó sì máa pa gbogbo àṣẹ mi mọ́, ẹ ó sì wá jẹ́ mímọ́ lójú Ọlọ́run+ yín. 41 Èmi ni Jèhófà Ọlọ́run yín, ẹni tó mú yín kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì, láti jẹ́ kí ẹ mọ̀ pé èmi ni Ọlọ́run+ yín. Èmi ni Jèhófà Ọlọ́run+ yín.’”
16 Kórà+ ọmọ Ísárì,+ ọmọ Kóhátì,+ ọmọ Léfì+ wá gbìmọ̀ pọ̀ pẹ̀lú Dátánì àti Ábírámù, àwọn ọmọ Élíábù+ pẹ̀lú Ónì ọmọ Péléétì, àwọn ọmọ Rúbẹ́nì.+ 2 Wọ́n dìtẹ̀ Mósè, àwọn àti igba ó lé àádọ́ta (250) ọkùnrin tó jẹ́ ọmọ Ísírẹ́lì, àwọn ìjòyè àpéjọ náà, àwọn tí a yàn nínú ìjọ, àwọn ọkùnrin tó lókìkí. 3 Wọ́n kóra jọ láti ta ko+ Mósè àti Áárónì, wọ́n sì sọ fún wọn pé: “Ó tó gẹ́ẹ́ yín! Gbogbo àpéjọ yìí jẹ́ mímọ́,+ gbogbo wọn pátá, Jèhófà sì wà láàárín wọn.+ Kí ló dé tí ẹ fi ń gbé ara yín ga lórí ìjọ Jèhófà?”
4 Nígbà tí Mósè gbọ́ èyí, ojú ẹsẹ̀ ló dojú bolẹ̀. 5 Ó sì sọ fún Kórà àti gbogbo àwọn tó ń tì í lẹ́yìn pé: “Tó bá di àárọ̀, Jèhófà máa jẹ́ ká mọ ẹni tó jẹ́ tirẹ̀+ àti ẹni tó jẹ́ mímọ́ àti ẹni tó gbọ́dọ̀ máa sún mọ́ ọn,+ ẹnikẹ́ni tó bá sì yàn+ ló máa sún mọ́ ọn. 6 Ohun tí ẹ máa ṣe nìyí: Kí ìwọ Kórà àti gbogbo àwọn tó ń tì ọ́ lẹ́yìn+ mú ìkóná,+ 7 kí ẹ fi iná sí i, kí ẹ sì fi tùràrí sí i níwájú Jèhófà lọ́la, ẹni tí Jèhófà bá sì yàn,+ òun ni ẹni mímọ́. “Ó tó gẹ́ẹ́, ẹ̀yin ọmọ Léfì!”+
8 Mósè wá sọ fún Kórà pé: “Ẹ jọ̀ọ́, ẹ fetí sílẹ̀ ẹ̀yin ọmọ Léfì. 9 Ṣé ohun kékeré lẹ rò pé Ọlọ́run Ísírẹ́lì ṣe fún yín, bó ṣe yà yín sọ́tọ̀ nínú àpéjọ Ísírẹ́lì,+ tó ń jẹ́ kí ẹ máa wá síwájú òun láti máa ṣiṣẹ́ nínú àgọ́ ìjọsìn Jèhófà, kí ẹ sì máa dúró níwájú àpéjọ láti máa ṣe ìránṣẹ́ fún wọn,+ 10 tó sì mú kí ìwọ àti gbogbo àwọn arákùnrin rẹ, àwọn ọmọ Léfì, sún mọ́ òun? Ṣé ó tún wá yẹ kí ẹ máa wá ọ̀nà láti gba iṣẹ́ àlùfáà?+ 11 Torí náà, ṣe ni ìwọ àti gbogbo àwọn tó wà lẹ́yìn rẹ tí ẹ kóra yín jọ ń bá Jèhófà jà. Kí wá ni ti Áárónì, tí ẹ fi ń kùn sí i?”+
12 Lẹ́yìn náà, Mósè ránṣẹ́ pe Dátánì àti Ábírámù,+ àwọn ọmọ Élíábù, àmọ́ wọ́n sọ pé: “A ò ní wá! 13 Ṣé ohun kékeré lo rò pé o ṣe, bí o ṣe mú wa kúrò ní ilẹ̀ tí wàrà àti oyin ti ń ṣàn, kí o lè wá pa wá sínú aginjù?+ Ṣé o tún wá fẹ́ sọ ara rẹ di ọba* lé wa lórí ni? 14 Títí di báyìí, o ò tíì mú wa dé ilẹ̀ kankan tí wàrà àti oyin ti ń ṣàn,+ bẹ́ẹ̀ lo ò fún wa ní ilẹ̀ àti ọgbà àjàrà kankan láti jogún. Ṣé o fẹ́ yọ ojú àwọn èèyàn yẹn ni? A ò ní wá!”
15 Inú bí Mósè gan-an, ó sì sọ fún Jèhófà pé: “Má bojú wo ọrẹ ọkà wọn. Mi ò gba kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ kankan lọ́wọ́ wọn, mi ò sì ṣe ìkankan nínú wọn léṣe.”+
16 Mósè wá sọ fún Kórà pé: “Kí ìwọ àti gbogbo àwọn tó ń tì ọ́ lẹ́yìn wá síwájú Jèhófà lọ́la, ìwọ, àwọn àti Áárónì. 17 Kí kálukú mú ìkóná rẹ̀, kó fi tùràrí sí i, kí ẹnì kọ̀ọ̀kan mú ìkóná rẹ̀ wá síwájú Jèhófà, kó jẹ́ igba ó lé àádọ́ta (250) ìkóná. Kí ìwọ àti Áárónì náà wà níbẹ̀, kí kálukú mú ìkóná rẹ̀ dání.” 18 Torí náà, ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn mú ìkóná rẹ̀, wọ́n sì fi iná àti tùràrí sí i, wọ́n dúró ní ẹnu ọ̀nà àgọ́ ìpàdé pẹ̀lú Mósè àti Áárónì. 19 Nígbà tí Kórà kó àwọn tó ń tì í lẹ́yìn,+ tí wọ́n jọ ń ta kò wọ́n jọ sí ẹnu ọ̀nà àgọ́ ìpàdé, ògo Jèhófà fara han gbogbo àpéjọ+ náà.
20 Jèhófà wá sọ fún Mósè àti Áárónì pé: 21 “Ẹ kúrò lọ́dọ̀ àwọn èèyàn yìí, kí n lè pa wọ́n run lẹ́ẹ̀kan náà.”+ 22 Ni wọ́n bá wólẹ̀, wọ́n sì sọ pé: “Ọlọ́run, ìwọ Ọlọ́run tó ni ẹ̀mí gbogbo èèyàn,*+ ṣé ẹ̀ṣẹ̀ ẹnì kan ṣoṣo máa wá mú kí o bínú sí gbogbo àpéjọ+ yìí?”
23 Jèhófà wá sọ fún Mósè pé: 24 “Sọ fún àwọn èèyàn náà pé, ‘Ẹ kúrò nítòsí àgọ́ Kórà, Dátánì àti Ábírámù!’”+
25 Ni Mósè bá gbéra, ó lọ bá Dátánì àti Ábírámù, àwọn àgbààgbà+ Ísírẹ́lì sì tẹ̀ lé e. 26 Ó sọ fún àpéjọ náà pé: “Ẹ jọ̀ọ́, ẹ kúrò nítòsí àgọ́ àwọn ọkùnrin burúkú yìí, ẹ má sì fara kan ohunkóhun tó jẹ́ tiwọn, kí ẹ má bàa pa run nítorí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ wọn.” 27 Ojú ẹsẹ̀ ni wọ́n kúrò nítòsí àgọ́ Kórà, Dátánì àti Ábírámù ní gbogbo àyíká wọn. Dátánì àti Ábírámù sì jáde wá, wọ́n dúró sí ẹnu ọ̀nà àgọ́ wọn, pẹ̀lú àwọn ìyàwó wọn àti àwọn ọmọ wọn, títí kan àwọn ọmọ wọn kéékèèké.
28 Mósè wá sọ pé: “Èyí á jẹ́ kí ẹ mọ̀ pé Jèhófà ló rán mi ní gbogbo ohun tí mò ń ṣe yìí, kì í ṣe ohun tó kàn wù mí:* 29 Tó bá jẹ́ pé bí gbogbo èèyàn ṣe ń kú làwọn èèyàn yìí máa kú, tó bá sì jẹ́ irú ìyà ẹ̀ṣẹ̀ tí gbogbo aráyé ń jẹ làwọn náà máa jẹ, a jẹ́ pé Jèhófà kọ́ ló rán mi.+ 30 Àmọ́ bí Jèhófà bá ṣe ohun tó ṣàrà ọ̀tọ̀ sí wọn, tí ilẹ̀ lanu,* tó sì gbé àwọn àti gbogbo ohun tó jẹ́ tiwọn mì, tí wọ́n sì lọ sínú Isà Òkú* láàyè, ẹ ó mọ̀ dájú pé àwọn ọkùnrin yìí ti hùwà àfojúdi sí Jèhófà.”
31 Bó ṣe sọ gbogbo ọ̀rọ̀ yìí tán, ilẹ̀ tí wọ́n dúró lé là sí méjì.+ 32 Ilẹ̀ sì lanu,* ó gbé wọn mì pẹ̀lú agbo ilé wọn àti gbogbo àwọn èèyàn Kórà+ pẹ̀lú gbogbo ẹrù wọn. 33 Bí àwọn àti gbogbo èèyàn wọn ṣe lọ sínú Isà Òkú* láàyè nìyẹn, ilẹ̀ bò wọ́n mọ́lẹ̀, wọ́n sì pa run láàárín ìjọ+ náà. 34 Gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó yí wọn ká sì sá lọ nígbà tí wọ́n ń kígbe, wọ́n ń sọ pé: “Ẹ̀rù ń bà wá kí ilẹ̀ má lọ gbé àwa náà mì!” 35 Iná sì wá látọ̀dọ̀ Jèhófà,+ ó jó igba ó lé àádọ́ta (250) ọkùnrin tó ń sun tùràrí+ run.
36 Jèhófà wá sọ fún Mósè pé: 37 “Sọ fún Élíásárì ọmọ àlùfáà Áárónì pé kí ó kó àwọn ìkóná+ náà kúrò nínú iná, torí wọ́n jẹ́ mímọ́. Tún sọ fún un pé kó tú iná náà ká dáadáa. 38 Kí ẹ fi ìkóná àwọn èèyàn tó ṣẹ̀ tí wọ́n sì fi ẹ̀mí ara wọn dí i ṣe àwọn irin pẹlẹbẹ tí ẹ máa fi bo pẹpẹ,+ torí iwájú Jèhófà ni wọ́n mú un wá, ó sì ti di mímọ́. Kó máa jẹ́ àmì fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.”+ 39 Àlùfáà Élíásárì wá kó àwọn ìkóná tí wọ́n fi bàbà ṣe, èyí tí àwọn tó jóná náà mú wá, ó sì fi wọ́n rọ ohun tí wọ́n á fi máa bo pẹpẹ, 40 bí Jèhófà ṣe gbẹnu Mósè sọ fún un. Yóò máa rán àwọn ọmọ Ísírẹ́lì létí pé ẹnikẹ́ni tí kò tọ́ sí,* tí kì í ṣe ọmọ Áárónì kò gbọ́dọ̀ sún mọ́ tòsí láti sun tùràrí níwájú Jèhófà+ àti pé ẹnikẹ́ni ò gbọ́dọ̀ dà bíi Kórà àti àwọn tó ń tì í lẹ́yìn.+
41 Ní ọjọ́ kejì, gbogbo àpéjọ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tún bẹ̀rẹ̀ sí í kùn sí Mósè àti Áárónì+ pé: “Ẹ̀yin méjèèjì ti pa àwọn èèyàn Jèhófà.” 42 Nígbà tí àwọn èèyàn náà kóra jọ, tí wọ́n ń sọ̀rọ̀ sí Mósè àti Áárónì, wọ́n wá yíjú sí àgọ́ ìpàdé, wò ó! ìkùukùu* bo àgọ́ náà, ògo Jèhófà sì bẹ̀rẹ̀ sí í fara hàn.+
43 Mósè àti Áárónì wá lọ síwájú àgọ́ ìpàdé,+ 44 Jèhófà sì sọ fún Mósè pé: 45 “Ẹ̀yin méjèèjì, ẹ kúrò láàárín àpéjọ yìí, kí n lè pa wọ́n run lẹ́ẹ̀kan náà.”+ Ni wọ́n bá wólẹ̀.+ 46 Mósè wá sọ fún Áárónì pé: “Mú ìkóná, kí o fi iná sí i látorí pẹpẹ,+ kí o fi tùràrí sí i, kí o wá yára lọ sọ́dọ̀ àwọn èèyàn náà, kí o sì ṣe ètùtù fún wọn,+ torí pé Jèhófà ti bínú sí wọn gan-an. Àjàkálẹ̀ àrùn ti bẹ̀rẹ̀!” 47 Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, Áárónì mú un, bí Mósè ṣe sọ, ó sì sáré lọ sáàárín ìjọ náà, wò ó! àjàkálẹ̀ àrùn ti bẹ̀rẹ̀ sí í kọ lù wọ́n. Ó wá fi tùràrí sí ìkóná náà, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe ètùtù fún àwọn èèyàn náà. 48 Ó dúró síbẹ̀, láàárín àwọn òkú àtàwọn alààyè, àjàkálẹ̀ àrùn náà sì wá dáwọ́ dúró. 49 Iye àwọn tí àjàkálẹ̀ àrùn náà pa jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́rìnlá ó lé ọgọ́rùn-ún méje (14,700), yàtọ̀ sí àwọn tó kú torí ọ̀rọ̀ Kórà. 50 Nígbà tí Áárónì fi máa pa dà sọ́dọ̀ Mósè ní ẹnu ọ̀nà àgọ́ ìpàdé, àjàkálẹ̀ àrùn náà ti dáwọ́ dúró.
17 Jèhófà wá sọ fún Mósè pé: 2 “Bá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sọ̀rọ̀, kí o sì gba ọ̀pá kan ní agbo ilé kọ̀ọ̀kan, lọ́wọ́ ìjòyè agbo ilé+ kọ̀ọ̀kan, kí gbogbo rẹ̀ jẹ́ ọ̀pá méjìlá (12). Kí o kọ orúkọ kálukú sára ọ̀pá rẹ̀. 3 Kí o kọ orúkọ Áárónì sára ọ̀pá Léfì, torí pé olórí agbo ilé kọ̀ọ̀kan ló ni ọ̀pá kọ̀ọ̀kan. 4 Kó àwọn ọ̀pá náà lọ sínú àgọ́ ìpàdé níwájú Ẹ̀rí,+ níbi tí mo ti máa ń pàdé yín.+ 5 Ẹni tí ọ̀pá rẹ̀ bá rúwé* ni ẹni tí mo yàn,+ màá sì pa àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lẹ́nu mọ́ kí wọ́n má bàa kùn sí mi+ mọ́, bí wọ́n ṣe ń kùn sí ẹ̀yin náà.”+
6 Mósè wá bá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sọ̀rọ̀, gbogbo ìjòyè wọn sì fún un ní ọ̀pá, ọ̀pá kan fún ìjòyè agbo ilé kọ̀ọ̀kan, ó jẹ́ ọ̀pá méjìlá (12), ọ̀pá Áárónì sì wà lára àwọn ọ̀pá náà. 7 Mósè wá kó àwọn ọ̀pá náà síwájú Jèhófà nínú àgọ́ Ẹ̀rí.
8 Nígbà tí Mósè wọnú àgọ́ Ẹ̀rí lọ́jọ́ kejì, wò ó! ọ̀pá Áárónì tó fi ṣojú fún ilé Léfì ti rúwé,* ó hù, ó yọ òdòdó, àwọn èso álímọ́ńdì tó ti pọ́n sì yọ lórí rẹ̀. 9 Mósè wá kó gbogbo ọ̀pá náà kúrò níwájú Jèhófà lọ sọ́dọ̀ gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì. Wọ́n wò ó, kálukú sì mú ọ̀pá tirẹ̀.
10 Lẹ́yìn náà, Jèhófà sọ fún Mósè pé: “Dá ọ̀pá+ Áárónì pa dà síwájú Ẹ̀rí, kó máa wà níbẹ̀, kó lè jẹ́ àmì+ fún àwọn ọmọ ọlọ̀tẹ̀,+ kí wọ́n má bàa kùn sí mi mọ́, kí wọ́n má bàa kú.” 11 Lójú ẹsẹ̀, Mósè ṣe ohun tí Jèhófà pa láṣẹ fún un. Ó ṣe bẹ́ẹ̀ gẹ́lẹ́.
12 Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì wá sọ fún Mósè pé: “A máa kú báyìí, ó dájú pé a máa ṣègbé, gbogbo wa la máa ṣègbé! 13 Kódà, ẹnikẹ́ni tó bá sún mọ́ àgọ́ ìjọsìn Jèhófà máa kú!+ Ṣé bí gbogbo wa ṣe máa kú nìyẹn?”+
18 Jèhófà wá sọ fún Áárónì pé: “Ìwọ àti àwọn ọmọ rẹ àti agbo ilé bàbá rẹ pẹ̀lú rẹ ni yóò máa dáhùn fún ẹ̀ṣẹ̀ èyíkéyìí lòdì sí ibi mímọ́,+ ìwọ àti àwọn ọmọ rẹ pẹ̀lú rẹ ni yóò sì máa dáhùn fún ẹ̀ṣẹ̀ èyíkéyìí lòdì sí iṣẹ́ àlùfáà+ yín. 2 Kí o tún mú àwọn arákùnrin rẹ tí wọ́n jẹ́ ara ẹ̀yà Léfì sún mọ́ tòsí, ẹ̀yà baba ńlá rẹ, kí wọ́n lè dara pọ̀ mọ́ ọ, kí wọn sì máa bá ìwọ àti àwọn ọmọ rẹ ṣiṣẹ́+ níwájú àgọ́ Ẹ̀rí.+ 3 Kí wọ́n máa ṣe ojúṣe wọn fún ọ àti fún àgọ́ náà lódindi.+ Àmọ́, wọn ò gbọ́dọ̀ sún mọ́ àwọn ohun èlò ibi mímọ́ àti pẹpẹ kí ẹ̀yin tàbí àwọn má bàa kú.+ 4 Kí wọ́n dara pọ̀ mọ́ ọ, kí wọ́n sì máa ṣe ojúṣe wọn tó jẹ mọ́ àgọ́ ìpàdé àti gbogbo iṣẹ́ àgọ́ náà, ẹnikẹ́ni tí kò lẹ́tọ̀ọ́* sí i kò sì gbọ́dọ̀ sún mọ́ yín.+ 5 Kí ẹ máa ṣe ojúṣe yín tó jẹ mọ́ ibi mímọ́ + àti pẹpẹ,+ kí n má bàa tún bínú+ sí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì. 6 Èmi fúnra mi ti mú àwọn arákùnrin yín, àwọn ọmọ Léfì, látinú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, mo sì fi wọ́n ṣe ẹ̀bùn fún yín.+ A ti fi wọ́n fún Jèhófà kí wọ́n lè máa bójú tó iṣẹ́ tó jẹ mọ́ àgọ́ ìpàdé.+ 7 Ojúṣe ìwọ àti àwọn ọmọ rẹ ni láti máa ṣe iṣẹ́ àlùfáà tó jẹ mọ́ pẹpẹ àtàwọn ohun tó wà lẹ́yìn aṣọ ìdábùú,+ ẹ̀yin ni kí ẹ máa ṣe iṣẹ́ yìí.+ Mo ti fi iṣẹ́ àlùfáà ṣe ẹ̀bùn fún yín, ṣe ni kí ẹ pa+ ẹnikẹ́ni tí kò lẹ́tọ̀ọ́* sí i tó bá sún mọ́ tòsí.”
8 Jèhófà tún sọ fún Áárónì pé: “Èmi fúnra mi fi gbogbo ọrẹ tí wọ́n bá ṣe fún mi+ sí ìkáwọ́ rẹ. Mo ti fún ìwọ àti àwọn ọmọ rẹ lára gbogbo ohun mímọ́ tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì bá fi ṣe ọrẹ, kó jẹ́ ìpín+ yín títí lọ. 9 Èyí ló máa jẹ́ tìrẹ nínú ọrẹ mímọ́ jù lọ tí wọ́n fi iná sun: gbogbo ọrẹ tí wọ́n bá mú wá, títí kan àwọn ọrẹ ọkà+ wọn àtàwọn ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀+ wọn pẹ̀lú àwọn ẹbọ ẹ̀bi+ wọn tí wọ́n mú wá fún mi. Ohun mímọ́ jù lọ ló jẹ́ fún ìwọ àti àwọn ọmọ rẹ. 10 Inú ibi mímọ́ jù lọ ni kí o ti jẹ ẹ́.+ Gbogbo ọkùnrin ló lè jẹ ẹ́. Kó jẹ́ ohun mímọ́ fún ọ.+ 11 Ìwọ náà lo tún ni èyí: àwọn ẹ̀bùn tí wọ́n mú+ wá pẹ̀lú gbogbo ọrẹ fífì+ tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì bá mú wá. Mo ti fún ìwọ àtàwọn ọmọkùnrin rẹ àti àwọn ọmọbìnrin rẹ pẹ̀lú rẹ, kó jẹ́ ìpín+ yín títí lọ. Gbogbo ẹni tó mọ́ nínú ilé rẹ ló lè jẹ ẹ́.+
12 “Mo fún ọ+ ní gbogbo òróró tó dáa jù àti gbogbo wáìnì tuntun tó dáa jù àti ọkà, àkọ́so+ wọn, èyí tí wọ́n fún Jèhófà. 13 Àkọ́pọ́n gbogbo ohun tó bá so nílẹ̀ wọn, tí wọ́n bá mú wá fún Jèhófà yóò di tìrẹ.+ Gbogbo ẹni tó mọ́ nínú ilé rẹ ló lè jẹ ẹ́.
14 “Gbogbo ohun tí wọ́n bá yà sọ́tọ̀* ní Ísírẹ́lì yóò di tìrẹ.+
15 “Àkọ́bí gbogbo ohun alààyè,*+ tí wọ́n bá mú wá fún Jèhófà, ì báà jẹ́ èèyàn tàbí ẹranko, yóò di tìrẹ. Àmọ́, o gbọ́dọ̀ ra àkọ́bí èèyàn+ pa dà, kí o sì tún ra àkọ́bí àwọn ẹran tó jẹ́ aláìmọ́ pa dà.+ 16 Tó bá ti pé oṣù kan tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ, kí o san owó ìràpadà láti rà á pa dà, kí o san ṣékélì*+ fàdákà márùn-ún tí wọ́n dá lé e, kó jẹ́ ìwọ̀n ṣékélì ibi mímọ́.* Ó jẹ́ ogún (20) òṣùwọ̀n gérà.* 17 Akọ màlúù tó jẹ́ àkọ́bí tàbí akọ ọ̀dọ́ àgùntàn tó jẹ́ àkọ́bí tàbí àkọ́bí ewúrẹ́ nìkan ni kí o má rà pa dà.+ Wọ́n jẹ́ ohun mímọ́. Kí o wọ́n ẹ̀jẹ̀ wọn sórí pẹpẹ,+ kí o sì mú kí ọ̀rá wọn rú èéfín bí ọrẹ àfinásun tó máa mú òórùn dídùn* jáde sí Jèhófà.+ 18 Kí ẹran wọn di tìrẹ. Kó di tìrẹ+ bí igẹ̀ ọrẹ fífì àti bí ẹsẹ̀ ọ̀tún. 19 Gbogbo ọrẹ mímọ́ tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì bá mú wá fún Jèhófà+ ni mo ti fún ìwọ àti àwọn ọmọkùnrin rẹ àti àwọn ọmọbìnrin rẹ pẹ̀lú rẹ, kó jẹ́ ìpín+ yín títí lọ. Ó jẹ́ májẹ̀mú iyọ̀* tó máa wà títí lọ níwájú Jèhófà fún ìwọ àti àwọn ọmọ rẹ pẹ̀lú rẹ.”
20 Jèhófà ń bá ọ̀rọ̀ tó ń sọ fún Áárónì lọ pé: “O ò ní ní ogún ní ilẹ̀ wọn, o ò sì ní ní ilẹ̀ kankan tó máa jẹ́ ìpín rẹ+ láàárín wọn. Èmi ni ìpín rẹ àti ogún rẹ láàárín àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.+
21 “Wò ó, mo ti fún àwọn ọmọ Léfì ní gbogbo ìdá mẹ́wàá+ ní Ísírẹ́lì, kó jẹ́ ogún wọn torí iṣẹ́ tí wọ́n ń ṣe, iṣẹ́ àgọ́ ìpàdé. 22 Kí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì má ṣe sún mọ́ àgọ́ ìpàdé mọ́, àìjẹ́ bẹ́ẹ̀, wọ́n ti dẹ́ṣẹ̀, wọ́n á sì kú. 23 Àwọn ọmọ Léfì fúnra wọn ni kó máa ṣiṣẹ́ ní àgọ́ ìpàdé, àwọn sì ni kó máa dáhùn fún ẹ̀ṣẹ̀ wọn.+ Àṣẹ tó máa wà títí lọ jálẹ̀ gbogbo ìran yín ni pé wọn ò gbọ́dọ̀ ní ogún láàárín àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.+ 24 Torí mo ti fi ìdá mẹ́wàá tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì máa mú wá fún Jèhófà ṣe ogún fún àwọn ọmọ Léfì. Ìdí nìyẹn tí mo fi sọ fún wọn pé, ‘Wọn ò gbọ́dọ̀ ní ogún+ láàárín àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.’”
25 Jèhófà wá sọ fún Mósè pé: 26 “Sọ fún àwọn ọmọ Léfì pé, ‘Ẹ ó máa gba ìdá mẹ́wàá lọ́wọ́ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, èyí tí mo fún yín láti ọwọ́ wọn kó lè jẹ́ ogún+ yín, kí ẹ sì fi ìdá mẹ́wàá lára ìdá mẹ́wàá náà ṣe ọrẹ fún Jèhófà.+ 27 Ìyẹn ló máa jẹ́ ọrẹ yín, bí ọkà láti ibi ìpakà+ tàbí ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ ohun tó jáde láti ibi tí wọ́n ti ń fún wáìnì tàbí òróró. 28 Báyìí ni ẹ̀yin náà á ṣe máa mú ọrẹ wá fún Jèhófà látinú gbogbo ìdá mẹ́wàá tí ẹ bá gbà lọ́wọ́ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, látinú wọn ni kí ẹ ti máa fún àlùfáà Áárónì ní ọrẹ tí ẹ mú wá fún Jèhófà. 29 Kí ẹ mú gbogbo onírúurú ọrẹ wá fún Jèhófà látinú ohun tó dáa jù nínú gbogbo ẹ̀bùn tí wọ́n fún yín+ bí ohun mímọ́.’
30 “Kí o sì sọ fún wọn pé, ‘Tí ẹ bá fi èyí tó dáa jù nínú wọn ṣe ọrẹ, yóò jẹ́ ti àwọn ọmọ Léfì bí ohun tó wá láti ibi ìpakà àti ohun tó wá láti ibi tí wọ́n ti ń fún wáìnì tàbí òróró. 31 Ibikíbi ni ẹ̀yin àti agbo ilé yín ti lè jẹ ẹ́, torí èrè iṣẹ́ tí ẹ̀ ń ṣe ní àgọ́ ìpàdé+ ló jẹ́. 32 Ẹ ò ní dẹ́ṣẹ̀ tí ẹ bá ṣe bẹ́ẹ̀, tó bá ṣáà ti jẹ́ èyí tó dáa jù lẹ́ fi ṣe ọrẹ, ẹ ò sì gbọ́dọ̀ sọ àwọn ohun mímọ́ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì di aláìmọ́, àìjẹ́ bẹ́ẹ̀, ẹ máa kú.’”+
19 Jèhófà tún sọ fún Mósè àti Áárónì pé: 2 “Èyí ni àṣẹ tí Jèhófà pa, ‘Sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé kí wọ́n mú abo màlúù pupa wá fún ọ, kó jẹ́ èyí tí ara rẹ̀ dá ṣáṣá tí kò ní àbùkù+ kankan, tí wọn ò sì de àjàgà mọ́ rí. 3 Kí ẹ fún àlùfáà Élíásárì, kó mú un lọ sí ẹ̀yìn ibùdó, kí wọ́n sì pa á níṣojú rẹ̀. 4 Kí àlùfáà Élíásárì wá fi ìka rẹ̀ mú lára ẹ̀jẹ̀ ẹran náà, kó sì wọ́n ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ lẹ́ẹ̀méje, sí ọ̀ọ́kán iwájú àgọ́+ ìjọsìn. 5 Kí wọ́n wá sun màlúù náà níṣojú rẹ̀. Kí wọ́n sun+ awọ rẹ̀, ẹran rẹ̀ àti ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ pẹ̀lú ìgbẹ́ rẹ̀. 6 Kí àlùfáà wá mú igi kédárì, ewéko hísópù+ àti òwú aláwọ̀ rírẹ̀dòdò, kó sì jù ú sínú iná tí wọ́n ti ń sun màlúù náà. 7 Kí àlùfáà wá fọ aṣọ rẹ̀, kó sì fi omi wẹ ara rẹ̀,* lẹ́yìn náà, ó lè wá sínú ibùdó; àmọ́ àlùfáà náà máa jẹ́ aláìmọ́ títí di alẹ́.
8 “‘Kí ẹni tó sun màlúù náà fi omi fọ aṣọ rẹ̀, kó fi omi wẹ ara rẹ̀,* kó sì jẹ́ aláìmọ́ títí di alẹ́.
9 “‘Kí ọkùnrin kan tó mọ́ kó eérú màlúù+ náà jọ, kó sì kó o sí ibi tó mọ́ lẹ́yìn ibùdó, kí àpéjọ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tọ́jú rẹ̀, kí wọ́n sì máa bù ú sínú omi tí wọ́n á fi ṣe ìwẹ̀mọ́.+ Ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ ni. 10 Kí ẹni tó kó eérú màlúù náà jọ fọ aṣọ rẹ̀, kó sì jẹ́ aláìmọ́ títí di alẹ́.
“‘Kí èyí jẹ́ àṣẹ tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì àti àjèjì tí wọ́n jọ ń gbé á máa tẹ̀ lé títí lọ.+ 11 Ẹnikẹ́ni tó bá fara kan òkú èèyàn* máa jẹ́ aláìmọ́ fún ọjọ́ méje.+ 12 Kí onítọ̀hún fi omi náà* wẹ ara rẹ̀ mọ́ ní ọjọ́ kẹta, yóò sì di mímọ́ ní ọjọ́ keje. Àmọ́ tí kò bá wẹ ara rẹ̀ mọ́ ní ọjọ́ kẹta, kò ní di mímọ́ ní ọjọ́ keje. 13 Ẹnikẹ́ni tó bá fara kan òkú èèyàn èyíkéyìí* tí kò sì wẹ ara rẹ̀ mọ́ ti sọ àgọ́ ìjọsìn+ Jèhófà di aláìmọ́, ṣe ni kí ẹ pa ẹni* náà kúrò ní Ísírẹ́lì.+ Torí pé wọn ò tíì wọ́n omi ìwẹ̀mọ́ + sí i lára, ó ṣì jẹ́ aláìmọ́. Àìmọ́ rẹ̀ ṣì wà lára rẹ̀.
14 “‘Òfin tí ẹ máa tẹ̀ lé nìyí tí ẹnì kan bá kú sínú àgọ́: Ẹnikẹ́ni tó bá wọnú àgọ́ náà àti ẹnikẹ́ni tó ti wà nínú àgọ́ náà tẹ́lẹ̀ máa jẹ́ aláìmọ́ fún ọjọ́ méje. 15 Gbogbo ohun èlò tó wà ní ṣíṣí tí wọn ò fi ìdérí dé jẹ́ aláìmọ́.+ 16 Ẹnikẹ́ni tó bá wà ní pápá tó sì fara kan ẹni tí wọ́n fi idà pa tàbí òkú tàbí egungun èèyàn tàbí ibi ìsìnkú yóò jẹ́ aláìmọ́ fún ọjọ́ méje.+ 17 Kí wọ́n bá aláìmọ́ náà bù lára eérú ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ tí wọ́n sun, kí wọ́n fi sínú ohun èlò kan, kí wọ́n sì bu omi tó ń ṣàn sí i. 18 Lẹ́yìn náà, kí ẹnì kan tó mọ́+ mú ewéko hísópù,+ kó kì í bọ inú omi náà, kó sì wọ́n ọn sára àgọ́ náà àti gbogbo ohun èlò àti sára àwọn* tó wà níbẹ̀ àti sára ẹni tó fara kan egungun tàbí ẹni tí wọ́n pa tàbí òkú tàbí ibi ìsìnkú. 19 Kí ẹni tó mọ́ náà wọ́n ọn sára aláìmọ́ náà ní ọjọ́ kẹta àti ní ọjọ́ keje,+ kó sì wẹ̀ ẹ́ mọ́ kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ ní ọjọ́ keje; kó wá fọ aṣọ rẹ̀, kó sì fi omi wẹ̀, yóò sì di mímọ́ ní alẹ́.
20 “‘Àmọ́ tí ẹnì kan bá jẹ́ aláìmọ́, tí kò sì wẹ ara rẹ̀ mọ́, ṣe ni kí ẹ pa ẹni* náà kúrò láàárín ìjọ,+ torí ó ti sọ ibi mímọ́ Jèhófà di aláìmọ́. Aláìmọ́ ni torí wọn ò wọ́n omi ìwẹ̀mọ́ sí i lára.
21 “‘Kí èyí jẹ́ àṣẹ tí wọ́n á máa tẹ̀ lé títí lọ: Kí ẹni tó ń wọ́n omi ìwẹ̀mọ́+ fọ aṣọ rẹ̀, kí ẹni tó sì fara kan omi ìwẹ̀mọ́ jẹ́ aláìmọ́ títí di alẹ́. 22 Ohunkóhun tí ẹni tó jẹ́ aláìmọ́ bá fara kàn yóò di aláìmọ́, ẹni* tó bá sì fara kàn án yóò jẹ́ aláìmọ́ títí di alẹ́.’”+
20 Ní oṣù kìíní, gbogbo àpéjọ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì dé aginjù Síínì, àwọn èèyàn náà sì bẹ̀rẹ̀ sí í gbé ní Kádéṣì.+ Ibẹ̀ ni Míríámù+ kú sí, ibẹ̀ sì ni wọ́n sin ín sí.
2 Ó ṣẹlẹ̀ pé kò sí omi fún àpéjọ+ náà, wọ́n bá kóra jọ lòdì sí Mósè àti Áárónì. 3 Àwọn èèyàn náà ń bá Mósè+ jà, wọ́n ń sọ pé: “Ó sàn ká ti kú nígbà tí àwọn arákùnrin wa kú níwájú Jèhófà! 4 Kí ló dé tí ẹ mú ìjọ Jèhófà wá sínú aginjù yìí kí àwa àtàwọn ẹran ọ̀sìn wa lè kú síbí?+ 5 Kí ló dé tí ẹ kó wa kúrò ní Íjíbítì wá sí ibi burúkú yìí?+ Irúgbìn, ọ̀pọ̀tọ́, àjàrà àti pómégíránétì ò lè hù níbí, bẹ́ẹ̀ ni kò sí omi tá a lè mu.”+ 6 Mósè àti Áárónì wá kúrò níwájú ìjọ náà lọ sí ẹnu ọ̀nà àgọ́ ìpàdé, wọ́n wólẹ̀, ògo Jèhófà sì bẹ̀rẹ̀ sí í fara hàn wọ́n.+
7 Jèhófà wá sọ fún Mósè pé: 8 “Mú ọ̀pá, kí ìwọ àti Áárónì ẹ̀gbọ́n rẹ sì pe àwọn èèyàn náà jọ, kí ẹ sì bá àpáta sọ̀rọ̀ níṣojú wọn kí omi lè jáde nínú rẹ̀, kí o fún wọn ní omi látinú àpáta náà, kí o sì fún àpéjọ náà àti ẹran ọ̀sìn wọn ní ohun tí wọ́n máa mu.”+
9 Mósè wá mú ọ̀pá náà níwájú Jèhófà+ bí Ó ṣe pa á láṣẹ fún un gẹ́lẹ́. 10 Lẹ́yìn náà, Mósè àti Áárónì pe ìjọ náà jọ síwájú àpáta náà, ó sì sọ fún wọn pé: “Ẹ gbọ́, ẹ̀yin ọlọ̀tẹ̀! Ṣé látinú àpáta+ yìí ni ká ti fún yín lómi ni?” 11 Ni Mósè bá gbé ọwọ́ rẹ̀ sókè, ó sì fi ọ̀pá rẹ̀ lu àpáta náà lẹ́ẹ̀mejì, omi púpọ̀ wá ń tú jáde, àpéjọ náà àtàwọn ẹran ọ̀sìn wọn sì bẹ̀rẹ̀ sí í mu ún.+
12 Lẹ́yìn náà, Jèhófà sọ fún Mósè àti Áárónì pé: “Torí pé ẹ ò fi hàn pé ẹ gbà mí gbọ́, ẹ ò sì fi hàn pé mo jẹ́ mímọ́ lójú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, ẹ ò ní mú ìjọ yìí dé ilẹ̀ tí màá fún wọn.”+ 13 Èyí ni omi Mẹ́ríbà,*+ ibẹ̀ ni àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ti bá Jèhófà jà, tó sì fi hàn wọ́n pé mímọ́ ni òun.
14 Mósè wá ní kí àwọn ìránṣẹ́ lọ láti Kádéṣì sọ́dọ̀ ọba Édómù+ pé: “Ohun tí Ísírẹ́lì+ arákùnrin rẹ sọ nìyí, ‘Gbogbo ìpọ́njú tó dé bá wa ni ìwọ náà mọ̀ dáadáa. 15 Àwọn bàbá wa lọ sí Íjíbítì,+ ọ̀pọ̀ ọdún*+ la sì fi gbé ní Íjíbítì, àwọn ará Íjíbítì sì fìyà jẹ àwa àti àwọn bàbá wa.+ 16 Nígbẹ̀yìn-gbẹ́yín, a ké pe Jèhófà,+ ó gbọ́ wa, ó sì rán áńgẹ́lì+ kan láti mú wa kúrò ní Íjíbítì, a ti wá dé Kádéṣì báyìí, ìlú tó wà ní ààlà ilẹ̀ rẹ. 17 Jọ̀ọ́, jẹ́ ká gba ilẹ̀ rẹ kọjá. A ò ní gba inú oko kankan tàbí ọgbà àjàrà, a ò sì ní mu omi kànga kankan. Ojú Ọ̀nà Ọba la máa gbà, a ò ní yà sí ọ̀tún tàbí sí òsì títí a fi máa kọjá ní ilẹ̀+ rẹ.’”
18 Àmọ́ Édómù sọ fún un pé: “Má gba ilẹ̀ wa kọjá. Tí o bá gbabẹ̀, idà ni màá wá fi pàdé rẹ.” 19 Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì fèsì pé: “Ojú pópó la máa gbà kọjá, tí àwa àtàwọn ẹran ọ̀sìn wa bá tiẹ̀ mu omi rẹ, a máa san owó rẹ̀.+ Kò sí nǹkan míì tá a fẹ́ ju pé ká fi ẹsẹ̀ wa rìn kọjá.”+ 20 Síbẹ̀ ó sọ pé: “O ò gbọ́dọ̀ kọjá.”+ Ni Édómù bá kó ọ̀pọ̀ èèyàn àti àwọn ọmọ ogun tó lágbára* jáde wá pàdé rẹ̀. 21 Bí Édómù kò ṣe jẹ́ kí Ísírẹ́lì gba ilẹ̀ òun kọjá nìyẹn; torí náà, Ísírẹ́lì yí pa dà lọ́dọ̀ rẹ̀.+
22 Gbogbo àpéjọ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì wá kúrò ní Kádéṣì, wọ́n sì wá sí Òkè Hóórì.+ 23 Jèhófà wá sọ fún Mósè àti Áárónì ní Òkè Hóórì létí ààlà ilẹ̀ Édómù pé: 24 “Wọ́n máa kó Áárónì jọ pẹ̀lú àwọn èèyàn rẹ̀.*+ Kò ní wọ ilẹ̀ tí màá fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, torí pé ẹ̀yin méjèèjì ṣe ohun tó lòdì sí àṣẹ tí mo pa nípa omi Mẹ́ríbà.+ 25 Mú Áárónì àti Élíásárì ọmọ rẹ̀, kí o sì mú wọn wá sí Òkè Hóórì. 26 Kí o bọ́ aṣọ+ ọrùn Áárónì, kí o sì wọ̀ ọ́ fún Élíásárì+ ọmọ rẹ̀, ibẹ̀ ni Áárónì máa kú sí.”*
27 Mósè wá ṣe ohun tí Jèhófà pa láṣẹ gẹ́lẹ́, wọ́n sì gun Òkè Hóórì lọ níṣojú gbogbo àpéjọ náà. 28 Mósè wá bọ́ aṣọ lọ́rùn Áárónì, ó sì wọ̀ ọ́ fún Élíásárì ọmọ rẹ̀. Lẹ́yìn náà, Áárónì kú síbẹ̀, lórí òkè+ náà. Mósè àti Élíásárì sì sọ̀ kalẹ̀ láti orí òkè náà. 29 Nígbà tí gbogbo àpéjọ náà wá rí i pé Áárónì ti kú, gbogbo ilé Ísírẹ́lì sunkún nítorí Áárónì fún ọgbọ̀n (30) ọjọ́.+
21 Nígbà tí ọba ìlú Árádì+ ti ilẹ̀ Kénáánì, tó ń gbé Négébù gbọ́ pé Ísírẹ́lì ti ń gba ọ̀nà Átárímù bọ̀, ó gbéjà ko Ísírẹ́lì, ó sì kó lára wọn lọ. 2 Ísírẹ́lì wá jẹ́ ẹ̀jẹ́ fún Jèhófà pé: “Tí o bá fi àwọn èèyàn yìí lé mi lọ́wọ́, ó dájú pé màá run àwọn ìlú wọn pátápátá.” 3 Jèhófà fetí sí ohùn Ísírẹ́lì, ó sì fi àwọn ọmọ Kénáánì lé wọn lọ́wọ́, wọ́n sì pa àwọn àti àwọn ìlú wọn run pátápátá. Wọ́n wá pe orúkọ ibẹ̀ ní Hóómà.*+
4 Bí wọ́n ṣe ń bá ìrìn àjò wọn lọ láti Òkè Hóórì,+ wọ́n gba ọ̀nà Òkun Pupa kọjá, kí wọ́n lè lọ gba ẹ̀yìn ilẹ̀ Édómù,+ ìrìn àjò náà sì tán àwọn èèyàn náà* lókun. 5 Àwọn èèyàn náà wá ń sọ̀rọ̀ sí Ọlọ́run àti Mósè+ pé: “Kí ló dé tí ẹ kó wa kúrò ní Íjíbítì ká lè wá kú sínú aginjù? Kò sí oúnjẹ, kò sí omi,+ a* sì ti kórìíra oúnjẹ játijàti+ yìí.”* 6 Ni Jèhófà bá rán àwọn ejò olóró* sí àwọn èèyàn náà, wọ́n sì ń ṣán àwọn èèyàn náà débi pé ọ̀pọ̀ lára àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ló kú.+
7 Àwọn èèyàn náà wá bá Mósè, wọ́n sì sọ pé: “A ti ṣẹ̀, torí a ti sọ̀rọ̀ sí Jèhófà àti ìwọ.+ Bá wa bẹ Jèhófà pé kó mú àwọn ejò náà kúrò lọ́dọ̀ wa.” Mósè sì bá àwọn èèyàn+ náà bẹ̀bẹ̀. 8 Jèhófà wá sọ fún Mósè pé: “Ṣe ejò kan tó dà bí ejò olóró,* kí o sì gbé e kọ́ sára òpó. Tí ejò bá ṣán ẹnikẹ́ni, onítọ̀hún máa ní láti wò ó kó má bàa kú.” 9 Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, Mósè fi bàbà ṣe ejò+ kan, ó sì gbé e kọ́ sára òpó+ náà. Nígbàkigbà tí ejò bá ṣán ẹnì kan, tó sì wo ejò bàbà náà, ẹni náà ò ní kú.+
10 Lẹ́yìn náà, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kúrò níbẹ̀, wọ́n sì pàgọ́ sí Óbótì.+ 11 Wọ́n kúrò ní Óbótì, wọ́n sì pàgọ́ sí Iye-ábárímù,+ ní aginjù tó dojú kọ Móábù, lápá ìlà oòrùn. 12 Wọ́n kúrò níbẹ̀, wọ́n sì pàgọ́ sí ẹ̀gbẹ́ Àfonífojì Séréédì.+ 13 Wọ́n kúrò níbẹ̀, wọ́n sì pàgọ́ sí agbègbè Áánónì,+ tó wà ní aginjù tó bẹ̀rẹ̀ láti ààlà àwọn Ámórì, torí Áánónì ni ààlà Móábù, láàárín Móábù àti àwọn Ámórì. 14 Ìdí nìyẹn tí ìwé Àwọn Ogun Jèhófà fi sọ̀rọ̀ nípa “Fáhébù tó wà ní Súfà àtàwọn àfonífojì Áánónì 15 àti gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́* àwọn àfonífojì, èyí tó dé ibi tí ìlú Árì wà, títí lọ dé ààlà Móábù.”
16 Lẹ́yìn náà, wọ́n lọ sí Bíà. Èyí ni kànga tí Jèhófà sọ nípa rẹ̀ fún Mósè pé: “Kó àwọn èèyàn náà jọ, kí n sì fún wọn ní omi.”
17 Ìgbà yẹn ni Ísírẹ́lì kọ orin yìí pé:
“Sun jáde, ìwọ kànga! Ẹ kọrin sí i!*
18 Kànga tí àwọn olórí gbẹ́, tí àwọn ìjòyè láàárín àwọn èèyàn wà,
Pẹ̀lú ọ̀pá àṣẹ àtàwọn ọ̀pá tiwọn.”
Wọ́n wá gbéra láti aginjù lọ sí Mátánà, 19 láti Mátánà, wọ́n lọ sí Náhálíélì, láti Náhálíélì, wọ́n lọ sí Bámótì.+ 20 Láti Bámótì, wọ́n lọ sí àfonífojì tó wà ní agbègbè* Móábù,+ ní òkè Písígà,+ tó kọjú sí Jéṣímónì.*+
21 Ísírẹ́lì wá ní kí àwọn ìránṣẹ́ lọ bá Síhónì ọba àwọn Ámórì pé:+ 22 “Jẹ́ ká gba ilẹ̀ rẹ kọjá. A ò ní yà sínú oko tàbí sínú ọgbà àjàrà. A ò ní mu omi inú kànga kankan. Ojú Ọ̀nà Ọba la máa gbà títí a fi máa kọjá ní ilẹ̀+ rẹ.” 23 Àmọ́ Síhónì ò jẹ́ kí Ísírẹ́lì gba ilẹ̀ rẹ̀ kọjá. Kàkà bẹ́ẹ̀, Síhónì kó gbogbo àwọn èèyàn rẹ̀ jọ, wọ́n sì lọ gbéjà ko Ísírẹ́lì ní aginjù, nígbà tí wọ́n dé Jáhásì, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í bá Ísírẹ́lì+ jà. 24 Àmọ́ Ísírẹ́lì fi idà+ ṣẹ́gun rẹ̀, ó sì gba ilẹ̀+ rẹ̀ láti Áánónì+ lọ dé Jábókù,+ nítòsí àwọn ọmọ Ámónì, torí pé ààlà àwọn ọmọ Ámónì+ ni Jásérì+ wà.
25 Bí Ísírẹ́lì ṣe gba gbogbo àwọn ìlú yìí nìyẹn, wọ́n wá ń gbé ní gbogbo ìlú àwọn Ámórì,+ ní Hẹ́ṣíbónì àti gbogbo àrọko rẹ̀.* 26 Torí Hẹ́ṣíbónì ni ìlú Síhónì ọba àwọn Ámórì, ẹni tó bá ọba Móábù jà, tó sì gba gbogbo ilẹ̀ rẹ̀ lọ́wọ́ rẹ̀ títí lọ dé Áánónì. 27 Ìdí nìyẹn tí àwọn kan fi máa ń sọ̀rọ̀ àbùkù yìí lówelówe pé:
“Wá sí Hẹ́ṣíbónì.
Jẹ́ ká kọ́ ìlú Síhónì, ká sì fìdí rẹ̀ múlẹ̀ gbọn-in.
28 Torí iná jáde wá láti Hẹ́ṣíbónì, ọwọ́ iná láti ìlú Síhónì.
Ó ti jó Árì ti Móábù run, àwọn olúwa àwọn ibi gíga Áánónì.
29 O gbé, ìwọ Móábù! Ẹ máa pa run, ẹ̀yin ará Kémóṣì!+
Ó sọ àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ di ìsáǹsá, ó sì sọ àwọn ọmọbìnrin rẹ̀ di ẹrú Síhónì, ọba àwọn Ámórì.
30 Ẹ jẹ́ ká ta wọ́n lọ́fà;
Hẹ́ṣíbónì máa pa run títí lọ dé Díbónì;+
Ẹ jẹ́ ká sọ ọ́ di ahoro títí dé Nófà;
Iná máa ràn dé Médébà.”+
31 Ísírẹ́lì wá ń gbé ní ilẹ̀ àwọn Ámórì. 32 Mósè rán àwọn ọkùnrin kan lọ ṣe amí Jásérì.+ Wọ́n gba àwọn àrọko rẹ̀,* wọ́n sì lé àwọn Ámórì tí wọ́n wà níbẹ̀ kúrò. 33 Lẹ́yìn náà, wọ́n pa dà, wọ́n sì lọ gba Ọ̀nà Báṣánì. Ógù+ ọba Báṣánì àti gbogbo àwọn èèyàn rẹ̀ sì jáde wá gbéjà kò wọ́n ní Édíréì.+ 34 Jèhófà sọ fún Mósè pé: “Má bẹ̀rù rẹ̀,+ torí màá fi òun àti gbogbo àwọn èèyàn rẹ̀ àti ilẹ̀ rẹ̀ lé ọ lọ́wọ́,+ ohun tí o ṣe sí Síhónì, ọba àwọn Ámórì tó gbé ní Hẹ́ṣíbónì+ gẹ́lẹ́ ni wàá ṣe sí i.” 35 Wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í bá òun àti àwọn ọmọ rẹ̀ àti gbogbo èèyàn rẹ̀ jà, títí ìkankan nínú àwọn èèyàn rẹ̀ ò fi ṣẹ́ kù,+ wọ́n sì gba ilẹ̀+ rẹ̀.
22 Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì wá gbéra, wọ́n sì pàgọ́ sí aṣálẹ̀ tó tẹ́jú ní Móábù, ní òdìkejì Jọ́dánì láti Jẹ́ríkò.+ 2 Bálákì+ ọmọ Sípórì ti rí gbogbo ohun tí Ísírẹ́lì ṣe sí àwọn Ámórì. 3 Ẹ̀rù àwọn èèyàn náà ba Móábù gan-an, torí wọ́n pọ̀ rẹpẹtẹ; kódà jìnnìjìnnì bá Móábù torí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.+ 4 Móábù wá sọ fún àwọn àgbààgbà Mídíánì+ pé: “Ìjọ yìí máa jẹ gbogbo ohun tó wà ní àyíká wa run, bí akọ màlúù ṣe máa ń jẹ ewéko inú pápá run.”
Bálákì ọmọ Sípórì ni ọba Móábù nígbà yẹn. 5 Ó ní kí àwọn ìránṣẹ́ lọ sọ́dọ̀ Báláámù ọmọ Béórì ní Pétórì,+ èyí tó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ Odò* ní ìlú ìbílẹ̀ rẹ̀. Ó sọ pé kí wọ́n pè é wá, ó ní: “Wò ó! Àwọn èèyàn kan ti wá láti Íjíbítì. Wò ó! Wọ́n bo ilẹ̀,*+ iwájú mi gan-an ni wọ́n sì ń gbé. 6 Torí náà, jọ̀ọ́ wá bá mi gégùn-ún+ fún àwọn èèyàn yìí, torí wọ́n lágbára jù mí lọ. Bóyá màá lè ṣẹ́gun wọn, kí n sì lé wọn kúrò ní ilẹ̀ náà, torí ó dá mi lójú pé ẹni tí o bá súre fún máa rí ìbùkún gbà, ègún sì máa wà lórí ẹni tí o bá gégùn-ún fún.”
7 Torí náà, àwọn àgbààgbà Móábù àtàwọn àgbààgbà Mídíánì mú owó ìwoṣẹ́ dání, wọ́n rìnrìn àjò lọ sọ́dọ̀ Báláámù,+ wọ́n sì jíṣẹ́ Bálákì fún un. 8 Ó wá sọ fún wọn pé: “Ẹ sùn síbí mọ́jú, ohunkóhun tí Jèhófà bá sọ fún mi, màá wá sọ fún yín.” Àwọn ìjòyè Móábù sì dúró sọ́dọ̀ Báláámù.
9 Ọlọ́run wá sọ́dọ̀ Báláámù, ó sì bi í pé:+ “Àwọn ọkùnrin wo ló wà lọ́dọ̀ rẹ yìí?” 10 Báláámù dá Ọlọ́run tòótọ́ lóhùn pé: “Bálákì ọmọ Sípórì, ọba Móábù ló ránṣẹ́ sí mi pé, 11 ‘Wò ó! Àwọn tó ń jáde bọ̀ láti Íjíbítì bo ilẹ̀.* Wá bá mi gégùn-ún fún wọn.+ Bóyá màá lè bá wọn jà, kí n sì lé wọn kúrò.’” 12 Àmọ́ Ọlọ́run sọ fún Báláámù pé: “O ò gbọ́dọ̀ tẹ̀ lé wọn lọ. O ò gbọ́dọ̀ gégùn-ún fún àwọn èèyàn náà, torí ẹni ìbùkún+ ni wọ́n.”
13 Nígbà tí ilẹ̀ mọ́, Báláámù dìde, ó sì sọ fún àwọn ìjòyè Bálákì pé: “Ẹ máa lọ sí ilẹ̀ yín, torí Jèhófà ò jẹ́ kí n bá yín lọ.” 14 Àwọn ìjòyè Móábù wá kúrò níbẹ̀, wọ́n sì pa dà sọ́dọ̀ Bálákì, wọ́n sọ fún un pé: “Báláámù ní òun ò ní tẹ̀ lé wa.”
15 Àmọ́ Bálákì tún rán àwọn ìjòyè míì tí wọ́n pọ̀, tí wọ́n sì tún kà sí pàtàkì ju àwọn ti àkọ́kọ́ lọ. 16 Wọ́n wá sọ́dọ̀ Báláámù, wọ́n sì sọ fún un pé: “Ohun tí Bálákì ọmọ Sípórì sọ nìyí, ‘Jọ̀ọ́, má ṣe jẹ́ kí ohunkóhun dí ọ lọ́wọ́ láti wá sọ́dọ̀ mi, 17 torí màá dá ọ lọ́lá gan-an, ohunkóhun tí o bá sì ní kí n ṣe ni màá ṣe. Torí náà, jọ̀ọ́ máa bọ̀, wá bá mi gégùn-ún fún àwọn èèyàn yìí.’” 18 Àmọ́ Báláámù dá àwọn ìránṣẹ́ Bálákì lóhùn pé: “Bí Bálákì bá tiẹ̀ fún mi ní ilé rẹ̀ tí fàdákà àti wúrà kún inú rẹ̀, mi ò ní ṣe ohunkóhun tó ta ko àṣẹ Jèhófà Ọlọ́run mi, bó ti wù kó kéré tàbí kó pọ̀ tó.+ 19 Àmọ́ ẹ jọ̀ọ́, ẹ tún sun ibí mọ́jú, kí n lè mọ ohun tí Jèhófà tún máa sọ fún mi.”+
20 Ọlọ́run wá bá Báláámù ní òru, ó sì sọ fún un pé: “Bó bá jẹ́ pé àwọn ọkùnrin yìí fẹ́ kí o tẹ̀ lé àwọn ni, tẹ̀ lé wọn. Àmọ́ ohun tí mo bá sọ fún ọ pé kí o sọ nìkan ni kí o sọ.”+ 21 Báláámù wá dìde nígbà tí ilẹ̀ mọ́, ó de ohun tí wọ́n fi ń jókòó mọ́ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́* rẹ̀,* ó sì tẹ̀ lé àwọn ìjòyè Móábù.+
22 Àmọ́ Ọlọ́run bínú sí i gidigidi torí pé ó ń lọ, áńgẹ́lì Jèhófà sì dúró ní ojú ọ̀nà láti dí i lọ́nà. Báláámù wà lórí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀, méjì lára àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ ni wọ́n sì jọ ń lọ. 23 Nígbà tí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà rí áńgẹ́lì Jèhófà tó dúró sójú ọ̀nà, tó ti fa idà yọ, kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà fẹ́ yà kúrò lọ́nà kó lè gba inú igbó. Àmọ́ Báláámù bẹ̀rẹ̀ sí í lu kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà kó lè dá a pa dà sójú ọ̀nà. 24 Áńgẹ́lì Jèhófà wá lọ dúró sí ọ̀nà tóóró kan láàárín ọgbà àjàrà méjì, ògiri olókùúta sì wà ní ẹ̀gbẹ́ méjèèjì. 25 Nígbà tí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà rí áńgẹ́lì Jèhófà, ó bẹ̀rẹ̀ sí í rún ara rẹ̀ mọ́ ògiri náà, ó sì gbá ẹsẹ̀ Báláámù mọ́ ògiri náà, Báláámù wá túbọ̀ ń lù ú.
26 Áńgẹ́lì Jèhófà tún wá kúrò níbẹ̀, ó sì lọ dúró ní ibi tóóró kan tí kò ti sí àyè láti yà sí ọ̀tún tàbí sí òsì. 27 Nígbà tí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà rí áńgẹ́lì Jèhófà, ó dùbúlẹ̀ lábẹ́ Báláámù, inú wá bí Báláámù gan-an, ó sì ń fi ọ̀pá rẹ̀ lu kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà. 28 Nígbẹ̀yìn-gbẹ́yín, Jèhófà mú kí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà sọ̀rọ̀,*+ ó sì sọ fún Báláámù pé: “Kí ni mo ṣe fún ọ tí o fi ń lù mí lẹ́ẹ̀mẹta+ yìí?” 29 Báláámù fún kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà lésì pé: “Torí o ti jẹ́ kí n máa ṣe bí òpònú ni. Ká ní idà wà lọ́wọ́ mi ni, ǹ bá ti pa ọ́ dà nù!” 30 Kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà wá sọ fún Báláámù pé: “Ṣebí èmi ni kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ tí o ti ń gùn ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ títí dòní? Ṣé mo ti ṣe báyìí sí ọ rí ni?” Ó dáhùn pé: “Rárá!” 31 Jèhófà wá la Báláámù lójú,+ ó sì rí áńgẹ́lì Jèhófà tó dúró sójú ọ̀nà, tó sì ti fa idà yọ. Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, ó tẹrí ba, ó sì dojú bolẹ̀.
32 Áńgẹ́lì Jèhófà wá sọ fún un pé: “Kí ló dé tí o fi lu kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ lẹ́ẹ̀mẹta yìí? Wò ó! Ṣe ni èmi fúnra mi jáde wá, kí n lè dí ọ lọ́nà, torí pé ohun tí o fẹ́ ṣe ta ko ohun tí mo fẹ́.+ 33 Kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà rí mi, ó sì fẹ́ yà fún mi lẹ́ẹ̀mẹta+ yìí. Ká ní kò yà fún mi ni, ǹ bá ti pa ọ́ báyìí! Màá sì dá kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà sí.” 34 Báláámù wá sọ fún áńgẹ́lì Jèhófà pé: “Mo ti ṣẹ̀, torí mi ò mọ̀ pé ìwọ lo dúró sójú ọ̀nà láti pàdé mi. Tó bá jẹ́ pé inú rẹ ò dùn sí i, màá pa dà.” 35 Àmọ́ áńgẹ́lì Jèhófà sọ fún Báláámù pé: “Máa tẹ̀ lé àwọn ọkùnrin náà lọ, àmọ́ ohun tí mo bá sọ fún ọ nìkan ni kí o sọ.” Báláámù wá ń bá àwọn ìjòyè Bálákì lọ.
36 Nígbà tí Bálákì gbọ́ pé Báláámù ti dé, ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ló lọ pàdé rẹ̀ ní ìlú Móábù, èyí tó wà ní etí Áánónì, ní ààlà ilẹ̀ náà. 37 Bálákì wá bi Báláámù pé: “Ṣebí mo ránṣẹ́ pè ọ́? Kí ló dé tó ò fi wá bá mi? Ṣó o rò pé mi ò lè dá ọ lọ́lá gan-an ni?”+ 38 Báláámù dá Bálákì lóhùn pé: “Ó dáa, mo ṣáà ti dé báyìí. Àmọ́ ṣé mo wá lè dá sọ ohunkóhun? Ọ̀rọ̀ tí Ọlọ́run bá fi sí mi lẹ́nu+ nìkan ni màá sọ.”
39 Báláámù wá tẹ̀ lé Bálákì lọ, wọ́n sì dé Kiriati-húsótì. 40 Bálákì fi màlúù àti àgùntàn rúbọ, ó sì fi lára rẹ̀ ránṣẹ́ sí Báláámù àtàwọn ìjòyè tó wà lọ́dọ̀ rẹ̀. 41 Nígbà tí ilẹ̀ mọ́, Bálákì mú Báláámù gòkè lọ sí Bamoti-báálì; ibẹ̀ ló ti rí gbogbo àwọn èèyàn náà.+
23 Báláámù wá sọ fún Bálákì pé: “Mọ pẹpẹ+ méje sí ibí yìí, kí o sì ṣètò akọ màlúù méje àti àgbò méje sílẹ̀ fún mi.” 2 Ojú ẹsẹ̀ ni Bálákì ṣe ohun tí Báláámù sọ gẹ́lẹ́. Bálákì àti Báláámù sì fi akọ màlúù kan àti àgbò kan rúbọ lórí pẹpẹ+ kọ̀ọ̀kan. 3 Báláámù wá sọ fún Bálákì pé: “Dúró síbí, nídìí ẹbọ sísun rẹ, èmi á sì lọ. Bóyá Jèhófà máa kàn sí mi. Màá jẹ́ kí o mọ ohunkóhun tó bá fi hàn mí.” Ó wá lọ sórí òkè kan tí ohunkóhun kò hù níbẹ̀.
4 Ọlọ́run kàn sí Báláámù,+ ó sì sọ fún Ọlọ́run pé: “Mo ti to pẹpẹ méje, mo sì ti fi akọ màlúù kan àti àgbò kan rúbọ lórí pẹpẹ kọ̀ọ̀kan.” 5 Jèhófà fi ọ̀rọ̀ yìí sí Báláámù+ lẹ́nu pé: “Pa dà sọ́dọ̀ Bálákì, ohun tí wàá sì sọ fún un nìyí.” 6 Ó wá pa dà, ó sì rí i pé Bálákì àti gbogbo ìjòyè Móábù dúró sí ẹ̀gbẹ́ ẹbọ sísun rẹ̀. 7 Ó wá sọ̀rọ̀ lówelówe pé:+
“Bálákì ọba Móábù mú mi wá láti Árámù,+
Láti àwọn òkè ìlà oòrùn:
‘Wá bá mi gégùn-ún fún Jékọ́bù.
Àní, wá dá Ísírẹ́lì lẹ́bi.’+
8 Ṣé kí n wá lọ gégùn-ún fún àwọn tí Ọlọ́run ò fi gégùn-ún ni?
Àbí kí n lọ dẹ́bi fún àwọn tí Jèhófà kò dá lẹ́bi?+
9 Mo rí wọn látorí àwọn àpáta,
Mo sì rí wọn látorí àwọn òkè.
10 Ta ló lè ka àwọn ọmọ Jékọ́bù+ tí wọ́n pọ̀ bí iyanrìn,
Ta ló tiẹ̀ lè ka ìdá mẹ́rin Ísírẹ́lì?
Jẹ́ kí n* kú ikú olódodo,
Sì jẹ́ kí ìgbẹ̀yìn mi rí bíi tiwọn.”
11 Bálákì wá sọ fún Báláámù pé: “Kí lo ṣe sí mi yìí? Mo mú ọ wá kí o lè gégùn-ún fún àwọn ọ̀tá mi, àmọ́ ṣe lo kàn wá ń súre fún wọn.”+ 12 Ó dá a lóhùn pé: “Ṣé kí n má sọ ohun tí Jèhófà bá fi sí mi lẹ́nu+ ni?”
13 Bálákì sọ fún un pé: “Jọ̀ọ́, jẹ́ ká lọ sí ibòmíì tí o ti lè rí wọn. Díẹ̀ nínú wọn ni wàá rí; o ò ní rí gbogbo wọn. Bá mi gégùn-ún fún wọn láti ibẹ̀.”+ 14 Torí náà, ó mú un lọ sí pápá Sófímù, ní orí Písígà,+ ó mọ pẹpẹ méje, ó sì fi akọ màlúù kan àti àgbò kan rúbọ lórí pẹpẹ+ kọ̀ọ̀kan. 15 Báláámù wá sọ fún Bálákì pé: “Dúró síbí, nídìí ẹbọ sísun rẹ, sì jẹ́ kí n kàn sí I níbẹ̀ yẹn.” 16 Jèhófà wá kàn sí Báláámù, ó sì fi ọ̀rọ̀ yìí sí i lẹ́nu+ pé: “Pa dà sọ́dọ̀ Bálákì, ohun tí wàá sì sọ nìyí.” 17 Torí náà, ó wá sọ́dọ̀ rẹ̀, ó sì rí i pé ó dúró ní ẹ̀gbẹ́ ẹbọ sísun rẹ̀, àwọn ìjòyè Móábù sì wà lọ́dọ̀ rẹ̀. Bálákì bi í pé: “Kí ni Jèhófà sọ?” 18 Ó wá sọ̀rọ̀ lówelówe pé:+
“Dìde Bálákì, kí o sì fetí sílẹ̀.
Tẹ́tí sí mi, ìwọ ọmọ Sípórì.
Tó bá sọ ohun kan, ṣé kò ní ṣe é?
Tó bá sì sọ̀rọ̀, ǹjẹ́ kò ní mú un ṣẹ?+
21 Kò fàyè gba agbára òkùnkùn èyíkéyìí láti bá Jékọ́bù jà,
Kò sì gbà kí wàhálà kankan dé bá Ísírẹ́lì.
Jèhófà Ọlọ́run rẹ̀ wà pẹ̀lú wọn,+
Wọ́n sì ń pòkìkí rẹ̀ bí ọba láàárín wọn.
22 Ọlọ́run ń mú wọn kúrò ní Íjíbítì.+
Ó dà bí ìwo akọ màlúù igbó fún wọn.+
Ní àkókò yìí, wọ́n á máa sọ nípa Jékọ́bù àti Ísírẹ́lì pé:
‘Ẹ wo ohun tí Ọlọ́run ṣe!’
24 Àwọn èèyàn yìí yóò dìde bíi kìnnìún,
Bíi kìnnìún ni yóò gbé ara rẹ̀ sókè.+
Kò ní dùbúlẹ̀ títí yóò fi jẹ ẹran tó bá mú
Tó sì máa mu ẹ̀jẹ̀ àwọn tó bá pa.”
25 Bálákì wá sọ fún Báláámù pé: “Tó ò bá ti lè gégùn-ún kankan fún un, kò tún yẹ kí o máa súre fún un.” 26 Báláámù fèsì pé: “Ṣebí mo ti sọ fún ọ pé, ‘Gbogbo ohun tí Jèhófà bá sọ ni màá ṣe’?”+
27 Bálákì sọ fún Báláámù pé: “Jọ̀ọ́ tẹ̀ lé mi, jẹ́ kí n tún mú ọ lọ sí ibòmíì. Bóyá Ọlọ́run tòótọ́ máa gbà pé kí o bá mi gégùn-ún fún un láti ibẹ̀.”+ 28 Bálákì wá mú Báláámù lọ sí orí òkè Péórì, tó dojú kọ Jéṣímónì.*+ 29 Báláámù wá sọ fún Bálákì pé: “Mọ pẹpẹ méje sí ibí yìí, kí o sì pèsè akọ màlúù méje àti àgbò méje sílẹ̀ fún mi.”+ 30 Bálákì wá ṣe ohun tí Báláámù sọ gẹ́lẹ́, ó sì fi akọ màlúù kan àti àgbò kan rúbọ lórí pẹpẹ kọ̀ọ̀kan.
24 Nígbà tí Báláámù wá rí i pé ó wu Jèhófà* láti súre fún Ísírẹ́lì, kò tún lọ wá bó ṣe máa ríran ìparun+ mọ́, àmọ́ ó yíjú sí aginjù. 2 Nígbà tí Báláámù wòkè tó sì rí i tí Ísírẹ́lì pàgọ́ wọn ní ẹ̀yà-ẹ̀yà,+ ẹ̀mí Ọlọ́run wá bà lé e.+ 3 Ó sì sọ̀rọ̀ lówelówe pé: +
“Ọ̀rọ̀ Báláámù ọmọ Béórì,
Àti ọ̀rọ̀ ẹnu ọkùnrin tí ojú rẹ̀ ti là,
4 Ọ̀rọ̀ ẹni tó ń gbọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run,
Tó rí ìran Olódùmarè,
Tó wólẹ̀ nígbà tí ojú rẹ̀ là:+
5 Àwọn àgọ́ rẹ mà rẹwà o, ìwọ Jékọ́bù,
Àwọn ibùgbé rẹ, ìwọ Ísírẹ́lì!+
6 Wọ́n tẹ́ lọ rẹrẹ+ bí àwọn àfonífojì,
Bí àwọn ọgbà tó wà létí odò,
Bí àwọn ewéko álóè tí Jèhófà gbìn,
Bí àwọn igi kédárì létí omi.
8 Ọlọ́run ń mú un kúrò ní Íjíbítì.
Ó dà bí ìwo akọ màlúù igbó fún wọn.
Ó máa jẹ àwọn orílẹ̀-èdè run, àwọn tó ń ni ín lára,+
Ó máa jẹ egungun wọn run, ó sì máa fi àwọn ọfà rẹ̀ run wọ́n.
9 Ó ti dùbúlẹ̀, ó sùn sílẹ̀ bíi kìnnìún,
Bíi kìnnìún, ta ló láyà láti jí i?
Ìbùkún ni fún àwọn tó ń súre fún ọ,
Ègún sì ni fún àwọn tó ń gégùn-ún+ fún ọ.”
10 Inú wá bí Bálákì sí Báláámù gan-an. Bálákì wá fi ìbínú pàtẹ́wọ́, ó sì sọ fún Báláámù pé: “Torí kí o lè gégùn-ún fún àwọn ọ̀tá mi ni mo ṣe pè ọ́ + wá, àmọ́ ṣe lo kàn ń súre fún wọn lẹ́ẹ̀mẹta yìí. 11 Ó yá, tètè pa dà sílé. Mo fẹ́ dá ọ lọ́lá gan-an+ tẹ́lẹ̀ ni, àmọ́ wò ó! Jèhófà ò jẹ́ kí n dá ọ lọ́lá.”
12 Báláámù dá Bálákì lóhùn pé: “Ṣebí mo sọ fún àwọn tí o rán pé, 13 ‘Bí Bálákì bá tiẹ̀ fún mi ní ilé rẹ̀ tí fàdákà àti wúrà kún inú rẹ̀, mi ò kàn ní ṣe ohunkóhun tó wù mí,* tó lòdì sí àṣẹ Jèhófà, bóyá ó dáa tàbí kò dáa. Ọ̀rọ̀ tí Jèhófà bá sọ fún mi nìkan ni màá sọ’?+ 14 Ní báyìí, mo fẹ́ pa dà sọ́dọ̀ àwọn èèyàn mi. Wá, jẹ́ kí n sọ fún ọ, ohun tí àwọn èèyàn yìí máa ṣe fún àwọn èèyàn rẹ lọ́jọ́ iwájú.”* 15 Ó wá sọ̀rọ̀ lówelówe pé:+
“Ọ̀rọ̀ Báláámù ọmọ Béórì,
Àti ọ̀rọ̀ ẹnu ọkùnrin tí ojú rẹ̀ ti là,+
16 Ọ̀rọ̀ ẹni tó ń gbọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run,
Àti ẹni tó ní ìmọ̀ Ẹni Gíga Jù Lọ,
Ó rí ìran Olódùmarè
Nígbà tó wólẹ̀, tí ojú rẹ̀ là:
17 Màá rí i, àmọ́ kì í ṣe báyìí;
Màá wò ó, àmọ́ kò tíì yá.
18 Édómù sì máa di ohun ìní,+
Àní, Séírì+ máa di ohun ìní àwọn ọ̀tá+ rẹ̀,
Bí Ísírẹ́lì ṣe ń fi hàn pé òun nígboyà.
19 Ẹnì kan yóò ti ọ̀dọ̀ Jékọ́bù wá, tí yóò máa ṣẹ́gun lọ,+
Yóò sì pa ẹnikẹ́ni tó bá yè bọ́ nínú ìlú náà run.”
20 Nígbà tó rí Ámálékì, ó ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ lówelówe pé:
21 Nígbà tó rí àwọn Kénì,+ ó ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ lówelówe pé:
“Ibùgbé rẹ ní ààbò, orí àpáta sì ni ilé rẹ fìkàlẹ̀ sí.
22 Àmọ́ ẹnì kan máa sun Kénì kanlẹ̀.
Ìgbà mélòó ló kù tí Ásíríà fi máa kó ọ lẹ́rú?”
23 Ó ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ lówelówe pé:
“Ó mà ṣe o! Ta ló máa yè bọ́ tí Ọlọ́run bá ṣe èyí?
24 Àwọn ọkọ̀ òkun máa wá láti etíkun Kítímù,+
25 Báláámù+ wá dìde, ó sì lọ, ó pa dà síbi tó ti wá. Bálákì náà sì bá ọ̀nà tirẹ̀ lọ.
25 Nígbà tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ń gbé ní Ṣítímù,+ wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í bá àwọn ọmọbìnrin Móábù+ ṣe ìṣekúṣe. 2 Àwọn obìnrin náà pè wọ́n síbi àwọn ẹbọ tí wọ́n ń rú sí àwọn ọlọ́run+ wọn, àwọn èèyàn náà wá bẹ̀rẹ̀ sí í jẹ, wọ́n sì ń forí balẹ̀ fún àwọn ọlọ́run+ wọn. 3 Bí Ísírẹ́lì ṣe bẹ̀rẹ̀ sí í bá wọn jọ́sìn* Báálì Péórì+ nìyẹn, inú sì bí Jèhófà gidigidi sí Ísírẹ́lì. 4 Torí náà, Jèhófà sọ fún Mósè pé: “Mú gbogbo àwọn olórí* nínú àwọn èèyàn yìí, kí o sì gbé wọn kọ́ síwájú Jèhófà ní ọ̀sán gangan,* kí inú tó ń bí Jèhófà gidigidi sí Ísírẹ́lì lè rọlẹ̀.” 5 Mósè wá sọ fún àwọn onídàájọ́ ní Ísírẹ́lì+ pé: “Kí kálukù yín pa àwọn èèyàn rẹ̀ tó bá wọn jọ́sìn* Báálì Péórì.”+
6 Ìgbà yẹn gan-an ni ọmọ Ísírẹ́lì kan wá mú obìnrin+ Mídíánì kan wá sí tòsí ibi tí àwọn èèyàn rẹ̀ wà, níṣojú Mósè àti gbogbo àpéjọ Ísírẹ́lì, nígbà tí wọ́n ń sunkún ní ẹnu ọ̀nà àgọ́ ìpàdé. 7 Nígbà tí Fíníhásì+ ọmọ Élíásárì ọmọ àlùfáà Áárónì rí i, ojú ẹsẹ̀ ló dìde láàárín àpéjọ náà, ó sì mú ọ̀kọ̀* kan dání. 8 Ló bá tẹ̀ lé ọkùnrin Ísírẹ́lì náà wọnú àgọ́, ó sì gún àwọn méjèèjì ní àgúnyọ, ó gún ọkùnrin Ísírẹ́lì náà àti obìnrin náà níbi ẹ̀yà ìbímọ rẹ̀. Bí àjàkálẹ̀ àrùn tó kọ lu àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe dáwọ́ dúró+ nìyẹn. 9 Iye àwọn tí àjàkálẹ̀ àrùn náà pa jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́rìnlélógún (24,000).+
10 Jèhófà wá sọ fún Mósè pé: 11 “Fíníhásì+ ọmọ Élíásárì ọmọ àlùfáà Áárónì ti jẹ́ kí inú tó ń bí mi sí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì rọlẹ̀ torí pé kò fàyè gba bíbá mi díje rárá láàárín wọn.+ Ìdí nìyẹn ti mi ò fi pa àwọn ọmọ Ísírẹ́lì run bó tiẹ̀ jẹ́ pé mo sọ fún wọn pé èmi nìkan ṣoṣo ni wọ́n gbọ́dọ̀ máa sìn.+ 12 Torí náà, sọ pé, ‘Màá bá a dá májẹ̀mú àlàáfíà. 13 Yóò sì jẹ́ májẹ̀mú iṣẹ́ àlùfáà tó máa wà pẹ́ títí fún òun àti àtọmọdọ́mọ rẹ̀,+ torí pé kò fàyè gba bíbá Ọlọ́run+ rẹ̀ díje, ó sì ṣe ètùtù fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.’”
14 Ó ṣẹlẹ̀ pé, orúkọ ọmọ Ísírẹ́lì tí wọ́n pa pẹ̀lú ọmọbìnrin Mídíánì náà ni Símírì ọmọ Sálù, ìjòyè agbo ilé bàbá àwọn ọmọ Síméónì. 15 Orúkọ obìnrin ọmọ Mídíánì tí wọ́n pa ni Kọ́síbì ọmọ Súúrì+ tó jẹ́ olórí àwọn agbo ilé, ní ìdílé kan ní Mídíánì.+
16 Jèhófà wá sọ fún Mósè pé: 17 “Ẹ lọ gbéjà ko àwọn ọmọ Mídíánì, kí ẹ sì ṣá wọn balẹ̀,+ 18 torí wọ́n ti ń dọ́gbọ́n gbéjà kò yín bí wọ́n ṣe fi ẹ̀tàn mú yín nínú ohun tó ṣẹlẹ̀ nínú ọ̀rọ̀ Péórì+ àti ọ̀rọ̀ Kọ́síbì ọmọ ìjòyè Mídíánì, arábìnrin wọn tí ẹ pa+ lọ́jọ́ tí àjàkálẹ̀ àrùn kọ lù yín torí ọ̀rọ̀ Péórì.”+
26 Lẹ́yìn tí àjàkálẹ̀ àrùn+ náà kásẹ̀ nílẹ̀, Jèhófà sọ fún Mósè àti Élíásárì ọmọ àlùfáà Áárónì pé: 2 “Ẹ ka gbogbo àpéjọ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì láti ẹni ogún (20) ọdún sókè, ní agbo ilé bàbá kọ̀ọ̀kan, kí ẹ ka gbogbo àwọn tó lè dara pọ̀ mọ́ àwọn ọmọ ogun Ísírẹ́lì.”+ 3 Mósè àti àlùfáà Élíásárì+ wá bá wọn sọ̀rọ̀ ní aṣálẹ̀ tó tẹ́jú ní Móábù,+ nítòsí Jọ́dánì ní Jẹ́ríkò+ pé: 4 “Ẹ kà wọ́n láti ẹni ogún (20) ọdún sókè, bí Jèhófà ṣe pa á láṣẹ fún Mósè.”+
Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tí wọ́n kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì nìyí: 5 Rúbẹ́nì,+ àkọ́bí Ísírẹ́lì; àwọn ọmọ+ Rúbẹ́nì nìyí: látọ̀dọ̀ Hánókù, ìdílé àwọn ọmọ Hánókù; látọ̀dọ̀ Pálù, ìdílé àwọn ọmọ Pálù; 6 látọ̀dọ̀ Hésírónì, ìdílé àwọn ọmọ Hésírónì; látọ̀dọ̀ Kámì, ìdílé àwọn ọmọ Kámì. 7 Ìwọ̀nyí ni ìdílé àwọn ọmọ Rúbẹ́nì, iye àwọn tí wọ́n sì forúkọ wọn sílẹ̀ jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́tàlélógójì ó lé ọgọ́rùn-ún méje àti ọgbọ̀n (43,730).+
8 Ọmọ Pálù ni Élíábù. 9 Àwọn ọmọ Élíábù ni: Némúẹ́lì, Dátánì àti Ábírámù. Dátánì àti Ábírámù yìí ni wọ́n yàn nínú àpéjọ náà, àwọn ló bá Mósè+ àti Áárónì jà pẹ̀lú àwọn tí Kórà kó jọ+ nígbà tí wọ́n bá Jèhófà+ jà.
10 Ilẹ̀ lanu,* ó sì gbé wọn mì. Ní ti Kórà, òun àtàwọn tó ń tì í lẹ́yìn kú nígbà tí iná jó igba ó lé àádọ́ta (250) ọkùnrin+ run. Wọ́n wá di àpẹẹrẹ tó jẹ́ ìkìlọ̀.+ 11 Àmọ́, àwọn ọmọ Kórà kò kú.+
12 Àwọn ọmọ Síméónì+ nìyí ní ìdílé-ìdílé: látọ̀dọ̀ Némúẹ́lì, ìdílé àwọn ọmọ Némúẹ́lì; látọ̀dọ̀ Jámínì, ìdílé àwọn ọmọ Jámínì; látọ̀dọ̀ Jákínì, ìdílé àwọn ọmọ Jákínì; 13 látọ̀dọ̀ Síírà, ìdílé àwọn ọmọ Síírà; látọ̀dọ̀ Ṣéọ́lù, ìdílé àwọn ọmọ Ṣéọ́lù. 14 Ìwọ̀nyí ni ìdílé àwọn ọmọ Síméónì: ẹgbẹ̀rún méjìlélógún ó lé igba (22,200).+
15 Àwọn ọmọ Gádì+ nìyí ní ìdílé-ìdílé: látọ̀dọ̀ Séfónì, ìdílé àwọn ọmọ Séfónì; látọ̀dọ̀ Hágì, ìdílé àwọn ọmọ Hágì; látọ̀dọ̀ Ṣúnì, ìdílé àwọn ọmọ Ṣúnì; 16 látọ̀dọ̀ Ósínì, ìdílé àwọn ọmọ Ósínì; látọ̀dọ̀ Érì, ìdílé àwọn ọmọ Érì; 17 látọ̀dọ̀ Áródù, ìdílé àwọn ọmọ Áródù; látọ̀dọ̀ Árélì, ìdílé àwọn ọmọ Árélì. 18 Ìwọ̀nyí ni ìdílé àwọn ọmọ Gádì, iye àwọn tí wọ́n forúkọ wọn sílẹ̀ jẹ́ ẹgbẹ̀rún lọ́nà ogójì ó lé ọgọ́rùn-ún márùn-ún (40,500).+
19 Àwọn ọmọ Júdà+ ni Éérì àti Ónánì.+ Àmọ́ Éérì àti Ónánì kú sí ilẹ̀ Kénáánì.+ 20 Àwọn ọmọ Júdà nìyí ní ìdílé-ìdílé: látọ̀dọ̀ Ṣélà,+ ìdílé àwọn ọmọ Ṣélà; látọ̀dọ̀ Pérésì,+ ìdílé àwọn ọmọ Pérésì; látọ̀dọ̀ Síírà,+ ìdílé àwọn ọmọ Síírà. 21 Àwọn ọmọ Pérésì nìyí: látọ̀dọ̀ Hésírónì,+ ìdílé àwọn ọmọ Hésírónì; látọ̀dọ̀ Hámúlù,+ ìdílé àwọn ọmọ Hámúlù. 22 Ìwọ̀nyí ni ìdílé Júdà, iye àwọn tí wọ́n forúkọ wọn sílẹ̀ jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́rìndínlọ́gọ́rin ó lé ọgọ́rùn-ún márùn-ún (76,500).+
23 Àwọn ọmọ Ísákà+ nìyí ní ìdílé-ìdílé: látọ̀dọ̀ Tólà,+ ìdílé àwọn ọmọ Tólà; látọ̀dọ̀ Púfà, ìdílé àwọn Púnì; 24 látọ̀dọ̀ Jáṣúbù, ìdílé àwọn ọmọ Jáṣúbù; látọ̀dọ̀ Ṣímúrónì, ìdílé àwọn ọmọ Ṣímúrónì. 25 Ìwọ̀nyí ni ìdílé Ísákà, iye àwọn tí wọ́n forúkọ wọn sílẹ̀ jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́rìnlélọ́gọ́ta ó lé ọgọ́rùn-ún mẹ́ta (64,300).+
26 Àwọn ọmọ Sébúlúnì+ nìyí ní ìdílé-ìdílé: látọ̀dọ̀ Sérédì, ìdílé àwọn ọmọ Sérédì; látọ̀dọ̀ Élónì, ìdílé àwọn ọmọ Élónì; látọ̀dọ̀ Jálíẹ́lì, ìdílé àwọn ọmọ Jálíẹ́lì. 27 Ìwọ̀nyí ni ìdílé àwọn ọmọ Sébúlúnì, iye àwọn tí wọ́n forúkọ wọn sílẹ̀ jẹ́ ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́ta ó lé ọgọ́rùn-ún márùn-ún (60,500).+
28 Àwọn ọmọ Jósẹ́fù+ nìyí ní ìdílé-ìdílé: Mánásè àti Éfúrémù.+ 29 Àwọn ọmọ Mánásè+ nìyí: látọ̀dọ̀ Mákírù,+ ìdílé àwọn ọmọ Mákírù; Mákírù wá bí Gílíádì;+ látọ̀dọ̀ Gílíádì, ìdílé àwọn ọmọ Gílíádì. 30 Àwọn ọmọ Gílíádì nìyí: látọ̀dọ̀ Yésérì, ìdílé àwọn ọmọ Yésérì; látọ̀dọ̀ Hélékì, ìdílé àwọn ọmọ Hélékì; 31 látọ̀dọ̀ Ásíríélì, ìdílé àwọn ọmọ Ásíríélì; látọ̀dọ̀ Ṣékémù, ìdílé àwọn ọmọ Ṣékémù; 32 látọ̀dọ̀ Ṣẹ́mídà, ìdílé àwọn ọmọ Ṣẹ́mídà; látọ̀dọ̀ Héfà, ìdílé àwọn ọmọ Héfà. 33 Ó ṣẹlẹ̀ pé, Sélóféhádì ọmọ Héfà kò bímọ ọkùnrin, obìnrin+ nìkan ló bí, orúkọ àwọn ọmọbìnrin Sélóféhádì+ ni Málà, Nóà, Hógílà, Mílíkà àti Tírísà. 34 Ìwọ̀nyí ni ìdílé Mánásè, iye àwọn tí wọ́n forúkọ wọn sílẹ̀ jẹ́ ẹgbẹ̀rún méjìléláàádọ́ta ó lé ọgọ́rùn-ún méje (52,700).+
35 Èyí ni àwọn ọmọ Éfúrémù+ ní ìdílé-ìdílé: látọ̀dọ̀ Ṣútélà, ìdílé àwọn ọmọ Ṣútélà;+ látọ̀dọ̀ Békérì, ìdílé àwọn ọmọ Békérì; látọ̀dọ̀ Táhánì, ìdílé àwọn ọmọ Táhánì. 36 Èyí sì ni àwọn ọmọ Ṣútélà: látọ̀dọ̀ Éránì, ìdílé àwọn ọmọ Éránì. 37 Ìwọ̀nyí ni ìdílé àwọn ọmọ Éfúrémù, iye àwọn tí wọ́n forúkọ wọn sílẹ̀ jẹ́ ẹgbẹ̀rún méjìlélọ́gbọ̀n ó lé ọgọ́rùn-ún márùn-ún (32,500).+ Èyí ni àwọn ọmọ Jósẹ́fù ní ìdílé-ìdílé.
38 Àwọn ọmọ Bẹ́ńjámínì+ nìyí ní ìdílé-ìdílé: látọ̀dọ̀ Bélà,+ ìdílé àwọn ọmọ Bélà; látọ̀dọ̀ Áṣíbélì, ìdílé àwọn ọmọ Áṣíbélì; látọ̀dọ̀ Áhírámù, ìdílé àwọn ọmọ Áhírámù; 39 látọ̀dọ̀ Ṣẹ́fúfámù, ìdílé àwọn ọmọ Súfámù; látọ̀dọ̀ Húfámù, ìdílé àwọn ọmọ Húfámù. 40 Àwọn ọmọ Bélà ni Áádì àti Náámánì:+ látọ̀dọ̀ Áádì, ìdílé àwọn ọmọ Áádì; látọ̀dọ̀ Náámánì, ìdílé àwọn ọmọ Náámánì. 41 Èyí ni àwọn ọmọ Bẹ́ńjámínì ní ìdílé-ìdílé, iye àwọn tí wọ́n forúkọ wọn sílẹ̀ jẹ́ ẹgbẹ̀rún márùndínláàádọ́ta ó lé ọgọ́rùn-ún mẹ́fà (45,600).+
42 Èyí ni àwọn ọmọ Dánì+ ní ìdílé-ìdílé: látọ̀dọ̀ Ṣúhámù, ìdílé àwọn ọmọ Ṣúhámù. Èyí ni àwọn ìdílé Dánì ní ìdílé-ìdílé. 43 Gbogbo àwọn tí wọ́n forúkọ wọn sílẹ̀ nínú ìdílé àwọn ọmọ Ṣúhámù jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́rìnlélọ́gọ́ta ó lé ọgọ́rùn-ún mẹ́rin (64,400).+
44 Àwọn ọmọ Áṣérì+ nìyí ní ìdílé-ìdílé: látọ̀dọ̀ Ímúnà, ìdílé àwọn ọmọ Ímúnà; látọ̀dọ̀ Íṣífì, ìdílé àwọn ọmọ Íṣífì; látọ̀dọ̀ Bẹráyà, ìdílé àwọn ọmọ Bẹráyà; 45 nínú àwọn ọmọ Bẹráyà: látọ̀dọ̀ Hébà, ìdílé àwọn ọmọ Hébà; látọ̀dọ̀ Málíkíélì, ìdílé àwọn ọmọ Málíkíélì. 46 Orúkọ ọmọbìnrin Áṣérì ni Sírà. 47 Ìwọ̀nyí ni ìdílé àwọn ọmọ Áṣérì, iye àwọn tí wọ́n forúkọ wọn sílẹ̀ jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́tàléláàádọ́ta ó lé ọgọ́rùn-ún mẹ́rin (53,400).+
48 Àwọn ọmọ Náfútálì+ nìyí ní ìdílé-ìdílé: látọ̀dọ̀ Jáséélì, ìdílé àwọn ọmọ Jáséélì; látọ̀dọ̀ Gúnì, ìdílé àwọn ọmọ Gúnì; 49 látọ̀dọ̀ Jésérì, ìdílé àwọn ọmọ Jésérì; látọ̀dọ̀ Ṣílẹ́mù, ìdílé àwọn ọmọ Ṣílẹ́mù. 50 Èyí ni àwọn ìdílé Náfútálì ní ìdílé-ìdílé, iye àwọn tí wọ́n forúkọ wọn sílẹ̀ jẹ́ ẹgbẹ̀rún márùndínláàádọ́ta ó lé ọgọ́rùn-ún mẹ́rin (45,400).+
51 Gbogbo àwọn tí wọ́n forúkọ wọn sílẹ̀ nínú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì jẹ́ ọgbọ̀n ọ̀kẹ́ ó lé ẹgbẹ̀rún kan, ọgọ́rùn-ún méje àti ọgbọ̀n (601,730).+
52 Lẹ́yìn náà, Jèhófà sọ fún Mósè pé: 53 “Kí ẹ pín ilẹ̀ náà bí ogún láàárín àwọn èèyàn yìí bí ẹ ṣe to orúkọ+ wọn.* 54 Kí ẹ fi kún ogún tí ẹ máa pín fún àwùjọ tó bá pọ̀, kí ẹ sì dín ogún+ tí ẹ máa pín fún àwùjọ tó bá kéré kù. Bí iye àwọn tí wọ́n forúkọ wọn sílẹ̀ ní àwùjọ kọ̀ọ̀kan bá ṣe pọ̀ tó ni kí ogún wọn ṣe pọ̀ tó. 55 Àmọ́, kèké+ ni kí ẹ fi pín ilẹ̀ náà. Orúkọ ẹ̀yà àwọn bàbá wọn ni kí ẹ fi pín ogún fún wọn. 56 Kèké ni kí ẹ fi pinnu bí ẹ ṣe máa pín ogún kọ̀ọ̀kan, kí ẹ sì pín in láàárín àwọn àwùjọ tó pọ̀ àtàwọn àwùjọ tó kéré.”
57 Èyí ni àwọn tí wọ́n forúkọ wọn sílẹ̀ nínú àwọn ọmọ Léfì+ ní ìdílé-ìdílé: látọ̀dọ̀ Gẹ́ṣónì, ìdílé àwọn ọmọ Gẹ́ṣónì; látọ̀dọ̀ Kóhátì,+ ìdílé àwọn ọmọ Kóhátì; látọ̀dọ̀ Mérárì, ìdílé àwọn ọmọ Mérárì. 58 Àwọn ìdílé àwọn ọmọ Léfì nìyí: ìdílé àwọn ọmọ Líbínì,+ ìdílé àwọn ọmọ Hébúrónì,+ ìdílé àwọn ọmọ Máhílì,+ ìdílé àwọn ọmọ Múṣì,+ ìdílé àwọn ọmọ Kórà.
Kóhátì+ bí Ámúrámù.+ 59 Orúkọ ìyàwó Ámúrámù sì ni Jókébédì,+ ọmọ Léfì, tí ìyàwó rẹ̀ bí fún un ní Íjíbítì. Ó wá bí Áárónì àti Mósè àti Míríámù+ arábìnrin wọn fún Ámúrámù. 60 Áárónì bí Nádábù, Ábíhù, Élíásárì àti Ítámárì.+ 61 Àmọ́ Nádábù àti Ábíhù kú torí wọ́n rú ẹbọ tí kò tọ́ níwájú Jèhófà.+
62 Gbogbo àwọn tí wọ́n forúkọ wọn sílẹ̀ jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́tàlélógún (23,000), gbogbo wọn jẹ́ ọkùnrin láti ọmọ oṣù kan sókè.+ Wọn ò forúkọ wọn sílẹ̀ pẹ̀lú ti àwọn ọmọ Ísírẹ́lì,+ torí wọn ò fún wọn ní ogún kankan láàárín àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.+
63 Èyí ni àwọn tí Mósè àti àlùfáà Élíásárì forúkọ wọn sílẹ̀ nígbà tí wọ́n forúkọ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sílẹ̀ ní aṣálẹ̀ tó tẹ́jú ní Móábù, nítòsí Jọ́dánì ní Jẹ́ríkò. 64 Àmọ́ ìkankan nínú wọn kò sí lára àwọn tí Mósè àti àlùfáà Áárónì forúkọ wọn sílẹ̀ nígbà tí wọ́n ka iye àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní aginjù Sínáì.+ 65 Torí Jèhófà ti sọ nípa wọn pé: “Ó dájú pé inú aginjù+ ni wọ́n máa kú sí.” Ẹnikẹ́ni ò ṣẹ́ kù lára wọn àfi Kélẹ́bù ọmọ Jéfúnè àti Jóṣúà ọmọ Núnì.+
27 Àwọn ọmọ Sélóféhádì+ wá sí tòsí, Sélóféhádì yìí ni ọmọ Héfà, ọmọ Gílíádì, ọmọ Mákírù, ọmọ Mánásè, látọ̀dọ̀ àwọn ìdílé Mánásè ọmọ Jósẹ́fù. Orúkọ àwọn ọmọ Sélóféhádì ni Málà, Nóà, Hógílà, Mílíkà àti Tírísà. 2 Wọ́n dúró síwájú Mósè, àlùfáà Élíásárì, àwọn ìjòyè+ àti gbogbo àpéjọ náà ní ẹnu ọ̀nà àgọ́ ìpàdé, wọ́n sì sọ pé: 3 “Bàbá wa ti kú ní aginjù, àmọ́ kò sí lára àwọn tó gbìmọ̀ pọ̀ láti ta ko Jèhófà, àwọn tó ti Kórà+ lẹ́yìn. Torí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ ló ṣe kú, kò sì ní ọmọkùnrin kankan. 4 Kí ló dé tí orúkọ bàbá wa fi máa pa rẹ́ nínú ìdílé rẹ̀ torí pé kò bímọ ọkùnrin? Fún wa ní ohun ìní láàárín àwọn arákùnrin bàbá wa.” 5 Mósè wá mú ọ̀rọ̀ wọn tọ Jèhófà+ lọ.
6 Jèhófà sọ fún Mósè pé: 7 “Òótọ́ làwọn ọmọ Sélóféhádì sọ. Rí i pé o fún wọn ní ohun ìní tí wọ́n lè jogún láàárín àwọn arákùnrin bàbá wọn, kí o sì mú kí ogún bàbá wọn di tiwọn.+ 8 Kí o wá sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé, ‘Tí ọkùnrin kan bá kú láì bímọ ọkùnrin, kí ẹ jẹ́ kí ogún rẹ̀ di ti ọmọbìnrin rẹ̀. 9 Tí kò bá sì bímọ obìnrin, kí ẹ fún àwọn arákùnrin rẹ̀ ní ogún rẹ̀. 10 Tí kò bá sì ní arákùnrin, kí ẹ fún àwọn arákùnrin bàbá rẹ̀ ní ogún rẹ̀. 11 Tí bàbá rẹ̀ ò bá sì ní arákùnrin, kí ẹ fún mọ̀lẹ́bí rẹ̀ tó sún mọ́ ọn jù ní ogún rẹ̀, yóò sì di tirẹ̀. Èyí ni àṣẹ tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì á máa tẹ̀ lé láti ṣèdájọ́, bí Jèhófà ṣe pa á láṣẹ fún Mósè gẹ́lẹ́.’”
12 Jèhófà wá sọ fún Mósè pé: “Gun orí òkè Ábárímù+ yìí, kí o sì wo ilẹ̀ tí màá fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.+ 13 Tí o bá ti rí i, a máa kó ọ jọ pẹ̀lú àwọn èèyàn rẹ,*+ bíi ti Áárónì ẹ̀gbọ́n rẹ,+ 14 torí nígbà tí àpéjọ náà ń bá mi jà ní aginjù Síínì, ẹ ṣe ohun tó lòdì sí àṣẹ tí mo pa pé kí ẹ tipasẹ̀ omi+ náà fi hàn pé mo jẹ́ mímọ́ níṣojú wọn. Èyí ni omi Mẹ́ríbà+ tó wà ní Kádéṣì + ní aginjù Síínì.”+
15 Mósè wá sọ fún Jèhófà pé: 16 “Kí Jèhófà, Ọlọ́run tó ni ẹ̀mí gbogbo èèyàn* yan ọkùnrin kan ṣe olórí àpéjọ náà, 17 ẹni tí yóò máa jáde, tí yóò sì máa wọlé níwájú wọn, tí yóò máa darí wọn jáde, tí yóò sì máa kó wọn wọlé, kí àpéjọ àwọn èèyàn Jèhófà má bàa dà bí àwọn àgùntàn tí kò ní olùṣọ́.” 18 Jèhófà wá sọ fún Mósè pé: “Mú Jóṣúà ọmọ Núnì, ọkùnrin tí ẹ̀mí wà nínú rẹ̀, kí o sì gbé ọwọ́ rẹ lé e.+ 19 Kí o wá mú un dúró níwájú àlùfáà Élíásárì àti gbogbo àpéjọ, kí o sì fa iṣẹ́ lé e lọ́wọ́ níṣojú+ wọn. 20 Kí o sì fún un+ lára àṣẹ* tí o ní, kí gbogbo àpéjọ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lè máa gbọ́ tirẹ̀.+ 21 Á sì máa dúró níwájú àlùfáà Élíásárì, ẹni tí yóò máa bá a ṣe ìwádìí níwájú Jèhófà nípasẹ̀ ohun tí Úrímù+ bá sọ. Àṣẹ rẹ̀ ni wọ́n á máa tẹ̀ lé tí wọ́n bá ń jáde, àṣẹ rẹ̀ ni wọ́n á sì máa tẹ̀ lé tí wọ́n bá ń wọlé, òun àti gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pẹ̀lú gbogbo àpéjọ náà.”
22 Mósè ṣe ohun tí Jèhófà pa láṣẹ fún un gẹ́lẹ́. Ó mú Jóṣúà dúró níwájú àlùfáà Élíásárì àti níwájú gbogbo àpéjọ náà, 23 ó gbé ọwọ́ rẹ̀ lé e, ó sì fa iṣẹ́ lé e+ lọ́wọ́ bí Jèhófà ṣe gbẹnu Mósè+ sọ gẹ́lẹ́.
28 Jèhófà wá sọ fún Mósè pé: 2 “Pàṣẹ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé, ‘Kí ẹ rí i pé ẹ mú ọrẹ mi wá, oúnjẹ mi. Kí ẹ máa mú àwọn ọrẹ àfinásun mi tó máa mú òórùn dídùn* jáde fún mi wá ní àkókò rẹ̀.’+
3 “Kí o sì sọ fún wọn pé, ‘Ọrẹ àfinásun tí ẹ máa mú wá fún Jèhófà nìyí: kí ẹ máa mú akọ ọ̀dọ́ àgùntàn méjì tó jẹ́ ọlọ́dún kan tí ara wọn dá ṣáṣá wá lójoojúmọ́ láti fi rú ẹbọ sísun nígbà gbogbo.+ 4 Kí o mú akọ ọ̀dọ́ àgùntàn kan wá ní àárọ̀, kí o sì mú akọ ọ̀dọ́ àgùntàn kejì wá ní ìrọ̀lẹ́,*+ 5 pẹ̀lú ìyẹ̀fun kíkúnná tó jẹ́ ìdá mẹ́wàá òṣùwọ̀n eéfà* tí wọ́n pò mọ́ òróró tí wọ́n fún tó jẹ́ ìlàrin òṣùwọ̀n hínì* láti fi ṣe ọrẹ ọkà.+ 6 Ẹbọ sísun ìgbà gbogbo+ ni, èyí tí a fi lélẹ̀ ní Òkè Sínáì láti mú òórùn dídùn* jáde, ọrẹ àfinásun sí Jèhófà, 7 pẹ̀lú ọrẹ ohun mímu rẹ̀, ìlàrin òṣùwọ̀n hínì fún akọ ọ̀dọ́ àgùntàn+ kọ̀ọ̀kan. Da ohun mímu tó ní ọtí náà sínú ibi mímọ́ láti fi ṣe ọrẹ ohun mímu fún Jèhófà. 8 Kí o sì mú akọ ọ̀dọ́ àgùntàn kejì wá ní ìrọ̀lẹ́.* Kí o fi ṣe ọrẹ àfinásun tó ń mú òórùn dídùn*+ jáde sí Jèhófà, pẹ̀lú ọrẹ ọkà kan náà tí o mú wá láàárọ̀ àti ọrẹ ohun mímu rẹ̀.
9 “Àmọ́, ní ọjọ́ Sábáàtì,+ kí ọrẹ náà jẹ́ akọ ọ̀dọ́ àgùntàn méjì tó jẹ́ ọlọ́dún kan tí ara wọn dá ṣáṣá àti ìyẹ̀fun kíkúnná tó jẹ́ ìdá méjì nínú mẹ́wàá òṣùwọ̀n eéfà tí wọ́n pò mọ́ òróró láti fi ṣe ọrẹ ọkà, pẹ̀lú ọrẹ ohun mímu rẹ̀. 10 Èyí ni ẹbọ sísun ti Sábáàtì, pẹ̀lú ẹbọ sísun ìgbà gbogbo àti ọrẹ+ ohun mímu rẹ̀.
11 “‘Ní ìbẹ̀rẹ̀ oṣù kọ̀ọ̀kan,* kí ẹ mú akọ ọmọ màlúù méjì, àgbò kan àti akọ ọ̀dọ́ àgùntàn méje tí ara wọn dá ṣáṣá tí ọ̀kọ̀ọ̀kan jẹ́ ọlọ́dún kan+ wá láti fi rú ẹbọ sísun sí Jèhófà, 12 pẹ̀lú ìyẹ̀fun kíkúnná tó jẹ́ ìdá mẹ́ta nínú mẹ́wàá òṣùwọ̀n tí wọ́n pò mọ́ òróró láti fi ṣe ọrẹ ọkà + fún akọ màlúù kọ̀ọ̀kan àti ìyẹ̀fun kíkúnná tó jẹ́ ìdá méjì nínú mẹ́wàá òṣùwọ̀n tí wọ́n pò mọ́ òróró láti fi ṣe ọrẹ ọkà fún àgbò+ náà, 13 pẹ̀lú ìyẹ̀fun kíkúnná tó jẹ́ ìdá mẹ́wàá òṣùwọ̀n tí wọ́n pò mọ́ òróró láti fi ṣe ọrẹ ọkà fún akọ ọ̀dọ́ àgùntàn kọ̀ọ̀kan, láti fi rú ẹbọ sísun tó ń mú òórùn dídùn*+ jáde, ọrẹ àfinásun sí Jèhófà. 14 Kí ọrẹ ohun mímu wọn jẹ́ wáìnì ìdajì òṣùwọ̀n hínì fún akọ màlúù+ kan àti ìdá mẹ́ta òṣùwọ̀n hínì fún àgbò+ náà àti ìlàrin òṣùwọ̀n hínì fún akọ ọ̀dọ́ àgùntàn+ kan. Èyí ni ẹbọ sísun oṣooṣù fún oṣù kọ̀ọ̀kan, jálẹ̀ ọdún. 15 Bákan náà, kí ẹ mú ọmọ ewúrẹ́ kan wá láti fi rú ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ sí Jèhófà, ní àfikún sí ẹbọ sísun ìgbà gbogbo àti ọrẹ ohun mímu rẹ̀.
16 “‘Ọjọ́ kẹrìnlá oṣù kìíní ni kó jẹ́ ọjọ́ Ìrékọjá+ sí Jèhófà. 17 Tó bá sì di ọjọ́ kẹẹ̀ẹ́dógún oṣù yìí, àjọyọ̀ máa wà. Ọjọ́ méje+ ni kí ẹ fi jẹ búrẹ́dì aláìwú. 18 Àpéjọ mímọ́ máa wà ní ọjọ́ kìíní. Ẹ ò gbọ́dọ̀ ṣe iṣẹ́ agbára kankan. 19 Kí ẹ fi akọ ọmọ màlúù méjì, àgbò kan àti akọ ọ̀dọ́ àgùntàn méje tí ọ̀kọ̀ọ̀kan jẹ́ ọlọ́dún kan rú ẹbọ sísun, ọrẹ àfinásun sí Jèhófà. Àwọn ẹran tí ara wọn dá ṣáṣá+ ni kí ẹ mú wá. 20 Kí ẹ mú wọn wá pẹ̀lú ọrẹ ọkà wọn, ìyẹn ìyẹ̀fun tó kúnná tí wọ́n pò mọ́ òróró,+ ìdá mẹ́ta nínú mẹ́wàá òṣùwọ̀n fún akọ màlúù kan àti ìdá méjì nínú mẹ́wàá òṣùwọ̀n fún àgbò náà. 21 Kí o mú ìdá mẹ́wàá òṣùwọ̀n wá fún ọ̀kọ̀ọ̀kan akọ ọ̀dọ́ àgùntàn méje náà 22 àti ewúrẹ́ kan tí o máa fi rú ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ láti ṣe ètùtù fún yín. 23 Kí ẹ mú ìwọ̀nyí wá yàtọ̀ sí ẹbọ sísun àárọ̀, èyí tó wà lára ẹbọ sísun ìgbà gbogbo. 24 Bẹ́ẹ̀ náà ni kí ẹ ṣe máa mú nǹkan wọ̀nyí wá ní ọjọ́ kọ̀ọ̀kan fún ọjọ́ méje láti fi ṣe oúnjẹ,* ọrẹ àfinásun tó ń mú òórùn dídùn* jáde sí Jèhófà. Kí ẹ fi rúbọ pẹ̀lú ẹbọ sísun ìgbà gbogbo àti ọrẹ ohun mímu rẹ̀. 25 Ní ọjọ́ keje, kí ẹ ṣe àpéjọ mímọ́.+ Ẹ ò gbọ́dọ̀ ṣe iṣẹ́ agbára+ kankan.
26 “‘Ní ọjọ́ àkọ́pọ́n èso,+ tí ẹ bá mú ọrẹ ọkà tuntun wá fún Jèhófà,+ kí ẹ ṣe àpéjọ mímọ́ nígbà tí ẹ bá ń ṣe àsè àwọn ọ̀sẹ̀.+ Ẹ ò gbọ́dọ̀ ṣe iṣẹ́ agbára+ kankan. 27 Kí ẹ mú akọ ọmọ màlúù méjì wá pẹ̀lú àgbò kan àti akọ ọ̀dọ́ àgùntàn méje tí ọ̀kọ̀ọ̀kan jẹ́ ọlọ́dún kan+ láti fi rú ẹbọ sísun tó ń mú òórùn dídùn* jáde sí Jèhófà, 28 pẹ̀lú ìyẹ̀fun tó kúnná tí wọ́n pò mọ́ òróró láti fi ṣe ọrẹ ọkà, ìdá mẹ́ta nínú mẹ́wàá òṣùwọ̀n fún akọ màlúù kọ̀ọ̀kan, ìdá méjì nínú mẹ́wàá òṣùwọ̀n fún àgbò náà, 29 ìdá mẹ́wàá òṣùwọ̀n fún ọ̀kọ̀ọ̀kan akọ ọ̀dọ́ àgùntàn méje náà, 30 pẹ̀lú ọmọ ewúrẹ́ kan láti ṣe ètùtù fún yín.+ 31 Kí ẹ fi wọ́n rúbọ ní àfikún sí ẹbọ sísun ìgbà gbogbo àti ọrẹ ọkà rẹ̀. Pẹ̀lú àwọn ọrẹ ohun mímu wọn, kí àwọn ẹran+ náà jẹ́ èyí tí ara wọn dá ṣáṣá.
29 “‘Ní ọjọ́ kìíní oṣù keje, kí ẹ ṣe àpéjọ mímọ́. Ẹ kò gbọ́dọ̀ ṣe iṣẹ́ agbára + kankan. Kí ẹ fun kàkàkí+ ní ọjọ́ náà. 2 Kí ẹ mú akọ ọmọ màlúù kan wá pẹ̀lú àgbò kan àti akọ ọ̀dọ́ àgùntàn méje tí ọ̀kọ̀ọ̀kan jẹ́ ọlọ́dún kan láti fi rú ẹbọ sísun tó ń mú òórùn dídùn* jáde sí Jèhófà, kí ara gbogbo wọn dá ṣáṣá, 3 pẹ̀lú ìyẹ̀fun tó kúnná tí wọ́n pò mọ́ òróró láti fi ṣe ọrẹ ọkà wọn, ìdá mẹ́ta nínú mẹ́wàá òṣùwọ̀n eéfà fún akọ màlúù náà, ìdá méjì nínú mẹ́wàá òṣùwọ̀n fún àgbò náà, 4 pẹ̀lú ìdá mẹ́wàá òṣùwọ̀n fún ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn akọ ọ̀dọ́ àgùntàn méje náà 5 àti akọ ọmọ ewúrẹ́ kan fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ láti ṣe ètùtù fún yín. 6 Èyí jẹ́ àfikún sí ẹbọ sísun oṣooṣù àti ọrẹ ọkà+ rẹ̀ àti ẹbọ sísun ìgbà gbogbo àti ọrẹ ọkà+ rẹ̀, pẹ̀lú àwọn ọrẹ ohun mímu+ wọn, bí ẹ ṣe máa ń ṣe é, láti mú òórùn dídùn* jáde, ọrẹ àfinásun sí Jèhófà.
7 “‘Kí ẹ ṣe àpéjọ mímọ́+ ní ọjọ́ kẹwàá oṣù keje yìí, kí ẹ sì pọ́n ara yín* lójú. Ẹ kò gbọ́dọ̀ ṣe iṣẹ́ kankan.+ 8 Kí ẹ sì mú akọ ọmọ màlúù kan, àgbò kan, akọ ọ̀dọ́ àgùntàn méje tí ọ̀kọ̀ọ̀kan jẹ́ ọlọ́dún kan wá láti fi rú ẹbọ sísun tó ń mú òórùn dídùn* jáde sí Jèhófà, kí ara gbogbo wọn dá ṣáṣá.+ 9 Kí ọrẹ ọkà wọn sì jẹ́ ìyẹ̀fun tó kúnná tí wọ́n pò mọ́ òróró, ìdá mẹ́ta nínú mẹ́wàá òṣùwọ̀n fún akọ màlúù náà, ìdá méjì nínú mẹ́wàá òṣùwọ̀n fún àgbò náà, 10 ìdá mẹ́wàá òṣùwọ̀n fún ọ̀kọ̀ọ̀kan akọ ọ̀dọ́ àgùntàn méje náà, 11 pẹ̀lú ọmọ ewúrẹ́ kan láti fi rú ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, yàtọ̀ sí ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ fún ètùtù+ àti ẹbọ sísun ìgbà gbogbo àti ọrẹ ọkà rẹ̀, pẹ̀lú àwọn ọrẹ ohun mímu wọn.
12 “‘Ní ọjọ́ kẹẹ̀ẹ́dógún oṣù keje, kí ẹ ṣe àpéjọ mímọ́. Ẹ má ṣe iṣẹ́ agbára kankan, kí ẹ sì fi ọjọ́ méje+ ṣe àjọyọ̀ fún Jèhófà. 13 Kí ẹ mú akọ ọmọ màlúù mẹ́tàlá (13) wá pẹ̀lú àgbò méjì àti akọ ọ̀dọ́ àgùntàn mẹ́rìnlá (14) tí ọ̀kọ̀ọ̀kan jẹ́ ọlọ́dún kan láti fi rú ẹbọ sísun,+ ọrẹ àfinásun tó máa mú òórùn dídùn* jáde sí Jèhófà. Kí ara gbogbo wọn dá ṣáṣá.+ 14 Kí ọrẹ ọkà wọn sì jẹ́ ìyẹ̀fun tó kúnná tí wọ́n pò mọ́ òróró, ìdá mẹ́ta nínú mẹ́wàá òṣùwọ̀n fún ọ̀kọ̀ọ̀kan akọ màlúù mẹ́tàlá (13) náà, ìdá méjì nínú mẹ́wàá òṣùwọ̀n fún ọ̀kọ̀ọ̀kan àgbò méjì náà 15 àti ìdá mẹ́wàá òṣùwọ̀n fún ọ̀kọ̀ọ̀kan akọ ọ̀dọ́ àgùntàn mẹ́rìnlá (14) náà 16 àti ọmọ ewúrẹ́ kan láti fi rú ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, yàtọ̀ sí ẹbọ sísun ìgbà gbogbo, ọrẹ ọkà rẹ̀ àti ọrẹ ohun mímu+ rẹ̀.
17 “‘Ní ọjọ́ kejì, kí ẹ mú akọ ọmọ màlúù méjìlá (12) wá pẹ̀lú àgbò méjì àti akọ ọ̀dọ́ àgùntàn mẹ́rìnlá (14) tí ọ̀kọ̀ọ̀kan jẹ́ ọlọ́dún kan, kí ara gbogbo wọn dá ṣáṣá,+ 18 pẹ̀lú ọrẹ ọkà àti àwọn ọrẹ ohun mímu tó wà fún àwọn akọ màlúù, àwọn àgbò àti àwọn akọ ọ̀dọ́ àgùntàn bí wọ́n bá ṣe pọ̀ tó, bí ẹ ṣe máa ń ṣe é, 19 pẹ̀lú ọmọ ewúrẹ́ kan láti fi rú ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, yàtọ̀ sí ẹbọ sísun ìgbà gbogbo àti ọrẹ ọkà rẹ̀, pẹ̀lú àwọn ọrẹ ohun mímu+ wọn.
20 “‘Ní ọjọ́ kẹta, kí ẹ mú akọ màlúù mọ́kànlá (11) wá pẹ̀lú àgbò méjì àti akọ ọ̀dọ́ àgùntàn mẹ́rìnlá (14) tí ọ̀kọ̀ọ̀kan jẹ́ ọlọ́dún kan, kí ara gbogbo wọn dá ṣáṣá,+ 21 pẹ̀lú ọrẹ ọkà àti àwọn ọrẹ ohun mímu tó wà fún àwọn akọ màlúù, àwọn àgbò àti àwọn akọ ọ̀dọ́ àgùntàn bí wọ́n bá ṣe pọ̀ tó, bí ẹ ṣe máa ń ṣe é, 22 pẹ̀lú ewúrẹ́ kan láti fi rú ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, yàtọ̀ sí ẹbọ sísun ìgbà gbogbo àti ọrẹ ọkà rẹ̀ àti ọrẹ ohun mímu+ rẹ̀.
23 “‘Ní ọjọ́ kẹrin, kí ẹ mú akọ màlúù mẹ́wàá wá pẹ̀lú àgbò méjì àti akọ ọ̀dọ́ àgùntàn mẹ́rìnlá (14) tí ọ̀kọ̀ọ̀kan jẹ́ ọlọ́dún kan, kí ara gbogbo wọn dá ṣáṣá,+ 24 pẹ̀lú ọrẹ ọkà àti àwọn ọrẹ ohun mímu tó wà fún àwọn akọ màlúù, àwọn àgbò àti àwọn akọ ọ̀dọ́ àgùntàn bí wọ́n bá ṣe pọ̀ tó, bí ẹ ṣe máa ń ṣe é, 25 pẹ̀lú ọmọ ewúrẹ́ kan láti fi rú ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, yàtọ̀ sí ẹbọ sísun ìgbà gbogbo, ọrẹ ọkà rẹ̀ àti ọrẹ ohun mímu+ rẹ̀.
26 “‘Ní ọjọ́ karùn-ún, kí ẹ mú akọ màlúù mẹ́sàn-án wá pẹ̀lú àgbò méjì àti akọ ọ̀dọ́ àgùntàn mẹ́rìnlá (14) tí ọ̀kọ̀ọ̀kan jẹ́ ọlọ́dún kan, kí ara gbogbo wọn dá ṣáṣá,+ 27 pẹ̀lú ọrẹ ọkà àti àwọn ọrẹ ohun mímu tó wà fún àwọn akọ màlúù, àwọn àgbò àti àwọn akọ ọ̀dọ́ àgùntàn bí wọ́n bá ṣe pọ̀ tó, bí ẹ ṣe máa ń ṣe é, 28 pẹ̀lú ọmọ ewúrẹ́ kan láti fi rú ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, yàtọ̀ sí ẹbọ sísun ìgbà gbogbo àti ọrẹ ọkà rẹ̀ pẹ̀lú ọrẹ ohun mímu+ rẹ̀.
29 “‘Ní ọjọ́ kẹfà, kí ẹ mú akọ màlúù mẹ́jọ wá pẹ̀lú àgbò méjì àti akọ ọ̀dọ́ àgùntàn mẹ́rìnlá (14) tí ọ̀kọ̀ọ̀kan jẹ́ ọlọ́dún kan, kí ara gbogbo wọn dá ṣáṣá,+ 30 pẹ̀lú ọrẹ ọkà àti àwọn ọrẹ ohun mímu tó wà fún àwọn akọ màlúù, àwọn àgbò àti àwọn akọ ọ̀dọ́ àgùntàn bí wọ́n bá ṣe pọ̀ tó, bí ẹ ṣe máa ń ṣe é, 31 pẹ̀lú ọmọ ewúrẹ́ kan láti fi rú ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, yàtọ̀ sí ẹbọ sísun ìgbà gbogbo, ọrẹ ọkà rẹ̀ àti àwọn ọrẹ ohun mímu+ rẹ̀.
32 “‘Ní ọjọ́ keje, kí ẹ mú akọ màlúù méje wá pẹ̀lú àgbò méjì àti akọ ọ̀dọ́ àgùntàn mẹ́rìnlá (14) tí ọ̀kọ̀ọ̀kan jẹ́ ọlọ́dún kan, kí ara gbogbo wọn dá ṣáṣá,+ 33 pẹ̀lú ọrẹ ọkà àti àwọn ọrẹ ohun mímu tó wà fún àwọn akọ màlúù, àwọn àgbò àti àwọn akọ ọ̀dọ́ àgùntàn bí wọ́n bá ṣe pọ̀ tó, bí ẹ ṣe máa ń ṣe é, 34 pẹ̀lú ọmọ ewúrẹ́ kan láti fi rú ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, yàtọ̀ sí ẹbọ sísun ìgbà gbogbo, ọrẹ ọkà rẹ̀ àti ọrẹ ohun mímu+ rẹ̀.
35 “‘Ní ọjọ́ kẹjọ, kí ẹ ṣe àpéjọ ọlọ́wọ̀. Ẹ má ṣe iṣẹ́ agbára kankan.+ 36 Kí ẹ mú akọ màlúù kan wá pẹ̀lú àgbò kan àti akọ ọ̀dọ́ àgùntàn méje, tí ọ̀kọ̀ọ̀kan jẹ́ ọlọ́dún kan láti fi rú ẹbọ sísun, ọrẹ àfinásun tó máa mú òórùn dídùn* jáde sí Jèhófà, kí ara gbogbo wọn dá ṣáṣá,+ 37 pẹ̀lú ọrẹ ọkà àti àwọn ọrẹ ohun mímu tó wà fún àwọn akọ màlúù, àwọn àgbò àti àwọn akọ ọ̀dọ́ àgùntàn bí wọ́n bá ṣe pọ̀ tó, bí ẹ ṣe máa ń ṣe é, 38 pẹ̀lú ọmọ ewúrẹ́ kan láti fi rú ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, yàtọ̀ sí ẹbọ sísun ìgbà gbogbo àti ọrẹ ọkà rẹ̀, pẹ̀lú ọrẹ ohun mímu+ rẹ̀.
39 “‘Èyí ni àwọn ohun tí ẹ máa fi rúbọ sí Jèhófà nígbà àwọn àjọyọ̀+ yín àtìgbàdégbà, ní àfikún sí àwọn ọrẹ tí ẹ jẹ́jẹ̀ẹ́+ àti àwọn ọrẹ àtinúwá+ yín láti fi rú àwọn ẹbọ sísun+ yín àti àwọn ọrẹ ọkà+ yín pẹ̀lú àwọn ọrẹ ohun mímu+ yín àti àwọn ẹbọ ìrẹ́pọ̀+ yín.’” 40 Mósè sọ gbogbo ohun tí Jèhófà pa láṣẹ fún un fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì.
30 Lẹ́yìn náà, Mósè bá àwọn olórí+ ẹ̀yà àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sọ̀rọ̀ pé: “Ohun tí Jèhófà pa láṣẹ nìyí: 2 Tí ọkùnrin kan bá jẹ́jẹ̀ẹ́+ fún Jèhófà tàbí tó búra+ pé òun máa* yẹra fún nǹkan kan, kò gbọ́dọ̀ yẹ ọ̀rọ̀ rẹ̀.+ Gbogbo ohun tó jẹ́jẹ̀ẹ́ pé òun máa ṣe ni kó ṣe.+
3 “Tí obìnrin kan bá sì jẹ́jẹ̀ẹ́ fún Jèhófà tàbí tó jẹ́jẹ̀ẹ́ pé òun máa yẹra fún nǹkan kan nígbà tó ṣì kéré, tó ṣì ń gbé ní ilé bàbá rẹ̀, 4 tí bàbá rẹ̀ wá gbọ́ nípa ẹ̀jẹ́ rẹ̀ tàbí ẹ̀jẹ́ tó jẹ́ pé òun* máa yẹra fún nǹkan kan tí bàbá rẹ̀ kò sì lòdì sí i, kó san gbogbo ẹ̀jẹ́ náà, kó sì san gbogbo ẹ̀jẹ́ tó jẹ́ láti yẹra fún ohunkóhun. 5 Àmọ́ tí bàbá rẹ̀ ò bá fara mọ́ ọn nígbà tó gbọ́ pé ó ti jẹ́jẹ̀ẹ́ tàbí pé ó jẹ́jẹ̀ẹ́ láti yẹra fún nǹkan kan, kó má san ẹ̀jẹ́ náà. Jèhófà máa dárí jì í torí bàbá rẹ̀ ò fara mọ́ ọn.+
6 “Àmọ́ tó bá lọ ilé ọkọ nígbà tí kò tíì san ẹ̀jẹ́ rẹ̀ tàbí tí kò tíì mú ìlérí tó ṣe láìronú jinlẹ̀ ṣẹ, 7 tí ọkọ rẹ̀ sì wá gbọ́ nípa ẹ̀jẹ́ náà tí kò sì lòdì sí i lọ́jọ́ tó gbọ́, ó máa san àwọn ẹ̀jẹ́ rẹ̀ àti àwọn ẹ̀jẹ́ tó jẹ́ pé òun máa yẹra fún àwọn nǹkan kan. 8 Àmọ́ tí ọkọ rẹ̀ ò bá fara mọ́ ọn lọ́jọ́ tó gbọ́ nípa rẹ̀, ó lè ní kó má san ẹ̀jẹ́ náà tàbí kó má ṣe mú ìlérí tó ṣe+ láìronú jinlẹ̀ ṣẹ, Jèhófà sì máa dárí jì í.
9 “Àmọ́ tí opó tàbí obìnrin kan tí òun àti ọkọ rẹ̀ ti kọ ara wọn sílẹ̀ bá jẹ́jẹ̀ẹ́, ó gbọ́dọ̀ san gbogbo ẹ̀jẹ́ tó jẹ́.
10 “Àmọ́ tó bá jẹ́ pé obìnrin kan ti wà nílé ọkọ kó tó jẹ́ ẹ̀jẹ́ tàbí tó jẹ́jẹ̀ẹ́ pé òun máa yẹra fún nǹkan kan, 11 tí ọkọ rẹ̀ wá gbọ́ nípa rẹ̀, tí kò sì lòdì sí i tàbí kó wọ́gi lé e, ó gbọ́dọ̀ san gbogbo ẹ̀jẹ́ rẹ̀ tàbí ẹ̀jẹ́ èyíkéyìí tó jẹ́ pé òun máa yẹra fún ohunkóhun. 12 Àmọ́ lọ́jọ́ tí ọkọ rẹ̀ bá gbọ́ nípa ẹ̀jẹ́ èyíkéyìí tó jẹ́ tàbí ẹ̀jẹ́ èyíkéyìí tó jẹ́ pé òun máa yẹra fún ohunkóhun, tó sì wọ́gi lé e pátápátá, obìnrin náà ò ní san ẹ̀jẹ́ náà.+ Ọkọ rẹ̀ ti wọ́gi lé e, Jèhófà sì máa dárí jì í. 13 Tó bá jẹ́ ẹ̀jẹ́ èyíkéyìí tàbí tó búra pé òun máa fi nǹkan du ara òun,* kí ọkọ rẹ̀ fara mọ́ ọn tàbí kó wọ́gi lé e. 14 Àmọ́ tí ọkọ rẹ̀ ò bá lòdì sí i bí ọjọ́ ṣe ń gorí ọjọ́, ó ti fara mọ́ gbogbo ẹ̀jẹ́ rẹ̀ tàbí gbogbo ẹ̀jẹ́ tó jẹ́ pé òun máa fi nǹkan du ara òun. Ó fara mọ́ ọn torí kò ta kò ó lọ́jọ́ tó gbọ́ tó ń jẹ́jẹ̀ẹ́. 15 Àmọ́ tó bá wọ́gi lé e lẹ́yìn èyí, lẹ́yìn ọjọ́ tó gbọ́ tó ń jẹ́jẹ̀ẹ́, ọkùnrin náà máa jẹ̀bi+ lórí ọ̀rọ̀ obìnrin náà.
16 “Èyí ni àwọn ìlànà tí Jèhófà pa láṣẹ fún Mósè nípa ọkọ àti ìyàwó rẹ̀ àti nípa bàbá àti ọ̀dọ́mọbìnrin rẹ̀ tó ṣì ń gbé lọ́dọ̀ rẹ̀.”
31 Jèhófà wá sọ fún Mósè pé: 2 “Gbẹ̀san+ lára àwọn ọmọ Mídíánì+ torí ohun tí wọ́n ṣe fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì. Lẹ́yìn náà, a máa kó ọ jọ pẹ̀lú àwọn èèyàn rẹ.”*+
3 Mósè wá sọ fún àwọn èèyàn náà pé: “Ẹ jẹ́ kí àwọn ọkùnrin yín dira ogun kí wọ́n lè gbéjà ko* Mídíánì, kí wọ́n sì mú ẹ̀san Jèhófà wá sórí Mídíánì. 4 Kí ẹ mú ẹgbẹ̀rún kan (1,000) látinú ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan nínú gbogbo ẹ̀yà Ísírẹ́lì kí wọ́n lè di ẹgbẹ́ ọmọ ogun.” 5 Torí náà, wọ́n yan ẹgbẹ̀rún kan (1,000) látinú ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan nínú ẹgbẹẹgbẹ̀rún Ísírẹ́lì,+ wọ́n jẹ́ ẹgbẹ̀rún méjìlá (12,000) tó dira ogun.*
6 Mósè wá rán wọn lọ, ẹgbẹ̀rún kan (1,000) látinú ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan láti jagun, ó ní kí Fíníhásì+ ọmọ àlùfáà Élíásárì lọ pẹ̀lú àwọn ọmọ ogun náà. Ọwọ́ rẹ̀ ni àwọn ohun èlò mímọ́ àti àwọn kàkàkí+ ogun wà. 7 Wọ́n bá Mídíánì jagun, bí Jèhófà ṣe pa á láṣẹ fún Mósè gẹ́lẹ́, wọ́n sì pa gbogbo ọkùnrin. 8 Yàtọ̀ sí àwọn tí wọ́n pa, wọ́n tún pa àwọn ọba Mídíánì, ìyẹn Éfì, Rékémù, Súúrì, Húrì àti Rébà, àwọn ọba Mídíánì márààrún. Wọ́n tún fi idà pa Báláámù+ ọmọ Béórì. 9 Àmọ́ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kó àwọn obìnrin Mídíánì àti àwọn ọmọ wọn kéékèèké lẹ́rú. Wọ́n tún kó gbogbo ẹran ọ̀sìn wọn, gbogbo agbo ẹran wọn àti gbogbo ohun ìní wọn bọ̀ láti ogun. 10 Wọ́n sì fi iná sun gbogbo ìlú tí wọ́n gbé àti gbogbo ibùdó* wọn. 11 Wọ́n kó gbogbo ẹrù wọn àti gbogbo ohun tí wọ́n rí lójú ogun, àwọn èèyàn àti ẹranko. 12 Wọ́n wá kó àwọn tí wọ́n kó lẹ́rú, àwọn ẹrù àtàwọn ohun tí wọ́n rí lójú ogun wá sọ́dọ̀ Mósè àti àlùfáà Élíásárì àti àpéjọ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, wọ́n kó wọn wá sínú ibùdó ní aṣálẹ̀ tó tẹ́jú ní Móábù,+ nítòsí Jọ́dánì, ní Jẹ́ríkò.
13 Mósè àti àlùfáà Élíásárì àti gbogbo ìjòyè àpéjọ náà lọ pàdé wọn lẹ́yìn ibùdó. 14 Àmọ́ inú bí Mósè sí àwọn ọkùnrin tí wọ́n yàn ṣe olórí àwọn ọmọ ogún náà, àwọn olórí ẹgbẹẹgbẹ̀rún àti àwọn olórí ọgọ́rọ̀ọ̀rún tí wọ́n ti ogun dé. 15 Mósè bi wọ́n pé: “Kí ló dé tí ẹ dá ẹ̀mí gbogbo obìnrin sí? 16 Ẹ wò ó! Àwọn ló tẹ̀ lé ọ̀rọ̀ Báláámù láti sún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì hùwà àìṣòótọ́+ sí Jèhófà nínú ọ̀rọ̀ Péórì,+ tí àjàkálẹ̀ àrùn fi kọ lu àpéjọ Jèhófà.+ 17 Ó yá, ẹ pa gbogbo àwọn ọmọ wọn ọkùnrin, kí ẹ sì pa gbogbo obìnrin tó ti bá ọkùnrin lò pọ̀ rí. 18 Àmọ́ kí ẹ dá ẹ̀mí gbogbo àwọn ọ̀dọ́bìnrin tí kò tíì bá ọkùnrin+ lò pọ̀ sí. 19 Kí ẹ pàgọ́ sí ẹ̀yìn ibùdó fún ọjọ́ méje. Kí gbogbo ẹ̀yin tí ẹ ti pa èèyàn* àti gbogbo ẹ̀yin tí ẹ ti fara kan ẹni tí wọ́n pa+ wẹ ara yín+ mọ́ ní ọjọ́ kẹta àti ní ọjọ́ keje, ẹ̀yin àti àwọn tí ẹ kó lẹ́rú. 20 Kí ẹ sì wẹ ẹ̀ṣẹ̀ mọ́ kúrò lára gbogbo aṣọ, gbogbo ohun tí wọ́n fi awọ ṣe, gbogbo ohun tí wọ́n fi irun ewúrẹ́ ṣe àti gbogbo ohun tí wọ́n fi igi ṣe.”
21 Àlùfáà Élíásárì wá sọ fún àwọn ọmọ ogun tó lọ sójú ogun náà pé: “Èyí ni àṣẹ tí Jèhófà pa fún Mósè, 22 ‘Wúrà, fàdákà, bàbà, irin, tánganran àti òjé nìkan, 23 gbogbo nǹkan tí kò lè tètè jóná, ni kí ẹ kó sínú iná, yóò sì mọ́. Àmọ́ kí ẹ tún fi omi ìwẹ̀mọ́ wẹ̀ ẹ́ mọ́.+ Kí ẹ kó gbogbo nǹkan tó lè tètè jóná sínú omi. 24 Kí ẹ fọ àwọn aṣọ yín ní ọjọ́ keje, kí ẹ sì mọ́, lẹ́yìn náà, ẹ lè wá sínú ibùdó.’”+
25 Jèhófà wá sọ fún Mósè pé: 26 “Ka iye ẹrù tí wọ́n kó bọ̀ láti ogun, kí o ka iye èèyàn tí wọ́n kó lẹ́rú àtàwọn ẹran; ìwọ àti àlùfáà Élíásárì àti àwọn olórí agbo ilé bàbá wọn nínú àpéjọ náà ni kí ẹ jọ kà á. 27 Pín ẹrù tí wọ́n kó bọ̀ láti ogun sí méjì, kí ìdá kan jẹ́ ti àwọn ọmọ ogun tí wọ́n lọ jagun, kí ìdá kejì sì jẹ́ ti gbogbo àwọn yòókù nínú àpéjọ+ náà. 28 Kí o gba ọkàn* kọ̀ọ̀kan nínú ọgọ́rùn-ún márùn-ún (500) èèyàn, ọ̀wọ́ ẹran, kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ àti agbo ẹran lọ́wọ́ àwọn ọmọ ogun tí wọ́n lọ jagun, láti fi ṣe ìpín Jèhófà. 29 Kí ẹ gbà á látinú ìdajì tiwọn, kí ẹ sì fún àlùfáà Élíásárì láti fi ṣe ọrẹ+ fún Jèhófà. 30 Kí o gba ẹyọ kan nínú àádọ́ta (50) èèyàn, ọ̀wọ́ ẹran, kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, agbo ẹran àti gbogbo onírúurú ẹran ọ̀sìn látinú ìdajì tó jẹ́ ti àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, kí o sì fún àwọn ọmọ Léfì,+ tí wọ́n ń bójú tó iṣẹ́ tó jẹ mọ́ àgọ́ ìjọsìn+ Jèhófà.”
31 Mósè àti àlùfáà Élíásárì ṣe ohun tí Jèhófà pa láṣẹ fún Mósè gẹ́lẹ́. 32 Iye ẹrù tó kù lára àwọn ohun tí wọ́n kó bọ̀ láti ojú ogun jẹ́ ọ̀kẹ́ mẹ́rìnlélọ́gbọ̀n ó dín ẹgbẹ̀rún márùn-ún (675,000) nínú agbo ẹran, 33 ẹgbẹ̀rún méjìléláàádọ́rin (72,000) nínú ọ̀wọ́ ẹran 34 àti ẹgbẹ̀rún mọ́kànlélọ́gọ́ta (61,000) kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́. 35 Iye àwọn obìnrin* tí kò tíì bá ọkùnrin+ lò pọ̀ rí jẹ́ ẹgbẹ̀rún méjìlélọ́gbọ̀n (32,000). 36 Ìdajì tó jẹ́ ìpín àwọn tó lọ sójú ogun jẹ́ ọ̀kẹ́ mẹ́tàdínlógún ó dín ẹgbẹ̀rún méjì àti ọgọ́rùn-ún márùn-ún (337,500) nínú agbo ẹran. 37 Iye ẹran tó jẹ́ ìpín Jèhófà látinú agbo ẹran jẹ́ ọgọ́rùn-ún mẹ́fà ó lé márùndínlọ́gọ́rin (675). 38 Ọ̀wọ́ ẹran jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́rìndínlógójì (36,000), iye tó jẹ́ ìpín Jèhófà nínú rẹ̀ sì jẹ́ méjìléláàádọ́rin (72). 39 Iye kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ jẹ́ ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgbọ̀n ó lé ọgọ́rùn-ún márùn-ún (30,500), iye tó jẹ́ ìpín Jèhófà nínú rẹ̀ sì jẹ́ mọ́kànlélọ́gọ́ta (61). 40 Iye èèyàn* jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́rìndínlógún (16,000), iye tó jẹ́ ìpín Jèhófà nínú wọn sì jẹ́ èèyàn* méjìlélọ́gbọ̀n (32). 41 Mósè wá kó àwọn ìpín náà fún àlùfáà+ Élíásárì láti fi ṣe ọrẹ fún Jèhófà, bí Jèhófà ṣe pa á láṣẹ fún Mósè gẹ́lẹ́.
42 Látinú ìdajì tó jẹ́ ti àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, èyí tí Mósè yà sọ́tọ̀ lára ìpín àwọn ọkùnrin tó lọ jagun, 43 ìdajì agbo ẹran náà jẹ́ ọ̀kẹ́ mẹ́tàdínlógún ó dín ẹgbẹ̀rún méjì ààbọ̀ (337,500), 44 ti ọ̀wọ́ ẹran jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́rìndínlógójì (36,000), 45 ti àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ jẹ́ ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgbọ̀n ó lé ọgọ́rùn-ún márùn-ún (30,500), 46 ìdajì àwọn èèyàn* náà sì jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́rìndínlógún (16,000). 47 Mósè wá gba ẹyọ kan nínú àádọ́ta (50) èèyàn àti ẹranko látinú ìdajì tó jẹ́ ti àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, ó sì kó wọn fún àwọn ọmọ Léfì,+ tí wọ́n ń bójú tó àgọ́ ìjọsìn+ Jèhófà, bí Jèhófà ṣe pa á láṣẹ fún Mósè gẹ́lẹ́.
48 Lẹ́yìn náà, àwọn ọkùnrin tí wọ́n yàn ṣe olórí ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn ọmọ ogun,+ àwọn olórí ẹgbẹẹgbẹ̀rún àti àwọn olórí ọgọ́rọ̀ọ̀rún, wá sọ́dọ̀ Mósè, 49 wọ́n sì sọ fún un pé: “Àwọn ìránṣẹ́ rẹ ti ka iye àwọn jagunjagun tí wọ́n wà lábẹ́ wa, a ò wá ẹnikẹ́ni tì nínú wọn.+ 50 Torí náà, jẹ́ kí ẹnì kọ̀ọ̀kan wa mú ohun tó rí wá láti fi ṣe ọrẹ fún Jèhófà, ìyẹn àwọn ohun tí wọ́n fi wúrà ṣe, ẹ̀gbà ẹsẹ̀, ẹ̀gbà ọwọ́, òrùka àṣẹ, yẹtí àtàwọn ohun ọ̀ṣọ́ míì, láti fi ṣe ètùtù fún ara* wa níwájú Jèhófà.”
51 Mósè àti àlùfáà Élíásárì gba wúrà náà lọ́wọ́ wọn, gbogbo ohun ọ̀ṣọ́ náà. 52 Gbogbo wúrà tí wọ́n fi ṣe ọrẹ fún Jèhófà jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́rìndínlógún ó lé ọgọ́rùn-ún méje àti àádọ́ta (16,750) ṣékélì,* láti ọwọ́ àwọn olórí ẹgbẹẹgbẹ̀rún àti àwọn olórí ọgọ́rọ̀ọ̀rún. 53 Ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ọmọ ogun náà mú ẹrù bọ̀ láti ogun fún ara rẹ̀. 54 Mósè àti àlùfáà Élíásárì wá gba wúrà náà lọ́wọ́ àwọn olórí ẹgbẹẹgbẹ̀rún àti olórí ọgọ́rọ̀ọ̀rún, wọ́n sì kó o wá sínú àgọ́ ìpàdé, kó lè jẹ́ ohun ìrántí fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì níwájú Jèhófà.
32 Ó ṣẹlẹ̀ pé àwọn ọmọ Rúbẹ́nì+ àti àwọn ọmọ Gádì+ ní ẹran ọ̀sìn tó pọ̀ gan-an, wọ́n sì rí i pé ilẹ̀ Jásérì+ àti ilẹ̀ Gílíádì dáa fún àwọn ẹran ọ̀sìn. 2 Torí náà, àwọn ọmọ Gádì àti àwọn ọmọ Rúbẹ́nì lọ bá Mósè àti àlùfáà Élíásárì pẹ̀lú àwọn ìjòyè àpéjọ náà pé: 3 “Átárótì, Díbónì, Jásérì, Nímírà, Hẹ́ṣíbónì,+ Éléálè, Sébámù, Nébò+ àti Béónì,+ 4 àwọn ilẹ̀ tí Jèhófà bá àpéjọ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì+ ṣẹ́gun, dáa fún àwọn ẹran ọ̀sìn,+ ẹran ọ̀sìn àwa ìránṣẹ́ rẹ sì pọ̀ gan-an.” 5 Wọ́n ń bá ọ̀rọ̀ wọn lọ pé: “Tí a bá rí ojúure rẹ, jẹ́ kí ilẹ̀ yìí di ohun ìní àwa ìránṣẹ́ rẹ. Má ṣe jẹ́ ká sọdá Jọ́dánì.”
6 Mósè wá dá àwọn ọmọ Gádì àti àwọn ọmọ Rúbẹ́nì lóhùn pé: “Ṣé ẹ̀yin wá fẹ́ máa gbé níbí nígbà tí àwọn arákùnrin yín bá lọ jagun ni? 7 Kí ló dé tí ẹ fẹ́ kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, kí wọ́n má bàa sọdá lọ sí ilẹ̀ tó dájú pé Jèhófà máa fún wọn? 8 Ohun tí àwọn bàbá yín ṣe nìyẹn nígbà tí mo rán wọn láti Kadeṣi-báníà pé kí wọ́n lọ wo ilẹ̀+ náà. 9 Nígbà tí wọ́n gòkè lọ sí Àfonífojì Éṣíkólì,+ tí wọ́n sì rí ilẹ̀ náà, wọ́n kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, kí wọ́n má bàa lọ sí ilẹ̀ tí Jèhófà fẹ́ fún wọn.+ 10 Inú bí Jèhófà gidigidi ní ọjọ́ yẹn débi tó fi búra+ pé: 11 ‘Àwọn ọkùnrin tó kúrò ní Íjíbítì, láti ẹni ogún (20) ọdún sókè kò ní rí ilẹ̀ + tí mo búra pé màá fún Ábúráhámù, Ísákì àti Jékọ́bù,+ torí pé wọn ò fi gbogbo ọkàn wọn tọ̀ mí lẹ́yìn, 12 àfi Kélẹ́bù+ ọmọ Jéfúnè ọmọ Kénásì àti Jóṣúà+ ọmọ Núnì, torí pé wọ́n fi gbogbo ọkàn wọn tọ Jèhófà lẹ́yìn.’+ 13 Jèhófà bínú gidigidi sí Ísírẹ́lì, ó sì mú kí wọ́n fi ogójì (40) ọdún+ rìn kiri nínú aginjù, títí gbogbo ìran tó ń hùwà ibi lójú Jèhófà fi pa run.+ 14 Ẹ̀yin ìran ẹlẹ́ṣẹ̀ ti wá rọ́pò àwọn bàbá yín, ẹ̀ ń mú kí ìbínú Jèhófà tó ń jó fòfò túbọ̀ gbóná mọ́ Ísírẹ́lì. 15 Tí ẹ ò bá tẹ̀ lé e mọ́, ó dájú pé ó tún máa fi wọ́n sílẹ̀ nínú aginjù, ẹ sì máa mú kí gbogbo àwọn èèyàn yìí pa run.”
16 Lẹ́yìn náà, wọ́n wá bá a, wọ́n sì sọ fún un pé: “Jẹ́ ká fi òkúta kọ́ ilé síbí fún àwọn ẹran ọ̀sìn wa, ká sì kọ́ ìlú fún àwọn ọmọ wa. 17 Àwa máa dira ogun,+ a ó sì máa lọ níwájú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì títí a fi máa mú wọn dé àyè wọn, àmọ́ àwọn ọmọ wa á máa gbé inú àwọn ìlú olódi, kí àwọn tó ń gbé ilẹ̀ náà má bàa yọ wọ́n lẹ́nu. 18 A ò ní pa dà sí ilé wa títí ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ọmọ Ísírẹ́lì á fi gba ilẹ̀ wọn, tí yóò sì di tiwọn.+ 19 A ò ní bá wọn pín ogún ní òdìkejì Jọ́dánì àti ìkọjá rẹ̀, torí pé a ti gba ogún tiwa ní apá ìlà oòrùn Jọ́dánì.”+
20 Mósè dá wọn lóhùn pé: “Tí ẹ bá lè ṣe èyí: Kí ẹ gbé ohun ìjà yín níwájú Jèhófà láti jagun+ náà; 21 tí gbogbo yín bá sì gbé ohun ìjà, tí ẹ sọdá Jọ́dánì níwájú Jèhófà nígbà tó ń lé àwọn ọ̀tá rẹ̀ kúrò níwájú rẹ̀,+ 22 títí a fi máa gba ilẹ̀ náà níwájú Jèhófà,+ nígbà náà, ẹ lè pa dà,+ ẹ ò sì ní jẹ̀bi lọ́dọ̀ Jèhófà àti Ísírẹ́lì. Ilẹ̀ yìí á wá di tiyín níwájú Jèhófà.+ 23 Àmọ́ bí ẹ kò bá ṣe èyí, a jẹ́ pé ẹ máa ṣẹ Jèhófà. Tó bá sì wá rí bẹ́ẹ̀, ẹ ò ní lọ láìjìyà ẹ̀ṣẹ̀ yín. 24 Torí náà, ẹ lè kọ́ àwọn ìlú fún àwọn ọmọ yín àti ilé fún àwọn ẹran ọ̀sìn+ yín, àmọ́ ẹ gbọ́dọ̀ mú ìlérí yín ṣẹ.”
25 Àwọn ọmọ Gádì àti àwọn ọmọ Rúbẹ́nì wá dá Mósè lóhùn pé: “Ohun tí olúwa mi pa láṣẹ ni àwa ìránṣẹ́ rẹ máa ṣe gẹ́lẹ́. 26 Àwọn ọmọ wa, àwọn ìyàwó wa, àwọn àgbo ẹran wa àti gbogbo ẹran ọ̀sìn wa máa wà ní àwọn ìlú Gílíádì,+ 27 àmọ́ àwa ìránṣẹ́ rẹ máa sọdá, gbogbo ọkùnrin tó dira ogun láti lọ jagun níwájú Jèhófà,+ bí olúwa mi ṣe sọ.”
28 Mósè wá pàṣẹ fún àlùfáà Élíásárì nípa wọn, fún Jóṣúà ọmọ Núnì àti àwọn olórí agbo ilé bàbá wọn nínú ẹ̀yà àwọn ọmọ Ísírẹ́lì. 29 Mósè sọ fún wọn pé: “Tí àwọn ọmọ Gádì àti àwọn ọmọ Rúbẹ́nì bá bá yín sọdá Jọ́dánì, tí gbogbo ọkùnrin sì dira ogun níwájú Jèhófà, tí ẹ sì ṣẹ́gun ilẹ̀ náà, kí ẹ wá fún wọn ní ilẹ̀ Gílíádì kó lè di tiwọn.+ 30 Àmọ́ tí wọn ò bá gbé ohun ìjà, tí wọn ò sì bá yín sọdá, a jẹ́ pé wọ́n á máa gbé láàárín yín ní ilẹ̀ Kénáánì.”
31 Àwọn ọmọ Gádì àti àwọn ọmọ Rúbẹ́nì fèsì pé: “Ohun tí Jèhófà sọ fún àwa ìránṣẹ́ rẹ la máa ṣe. 32 A máa gbé ohun ìjà, a ó sì sọdá sí ilẹ̀ Kénáánì+ níwájú Jèhófà, àmọ́ apá ibi tá a wà ní Jọ́dánì yìí ni ogún wa máa wà.” 33 Mósè fún àwọn ọmọ Gádì, àwọn ọmọ Rúbẹ́nì+ àti ààbọ̀ ẹ̀yà Mánásè+ ọmọ Jósẹ́fù ní ilẹ̀ tí Síhónì+ ọba àwọn Ámórì ti ń jọba àti ilẹ̀ ti Ógù+ ọba Báṣánì ti ń jọba, ilẹ̀ tó wà láwọn ìlú rẹ̀ ní àwọn agbègbè yẹn àti àwọn ìlú tó yí ilẹ̀ náà ká.
34 Àwọn ọmọ Gádì kọ́* Díbónì,+ Átárótì,+ Áróérì,+ 35 Atiroti-ṣófánì, Jásérì,+ Jógíbéhà,+ 36 Bẹti-nímírà+ àti Bẹti-háránì,+ àwọn ìlú olódi, wọ́n sì fi òkúta kọ́ ilé fún àwọn agbo ẹran. 37 Àwọn ọmọ Rúbẹ́nì kọ́ Hẹ́ṣíbónì,+ Éléálè,+ Kíríátáímù,+ 38 Nébò+ àti Baali-méónì,+ wọ́n yí orúkọ àwọn ìlú náà pa dà, wọ́n kọ́ Síbúmà; wọ́n sì sọ àwọn ìlú tí wọ́n tún kọ́ ní orúkọ míì.
39 Àwọn ọmọ Mákírù+ ọmọ Mánásè lọ sí Gílíádì láti gbógun jà á, wọ́n gbà á, wọ́n sì lé àwọn Ámórì tó wà níbẹ̀ kúrò. 40 Torí náà, Mósè fún Mákírù ọmọ Mánásè ní Gílíádì, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í gbé ibẹ̀.+ 41 Jáírì ọmọ Mánásè lọ síbẹ̀ láti gbógun jà wọ́n, ó sì gba àwọn abúlé tí wọ́n pàgọ́ sí, ó wá pè wọ́n ní Hafotu-jáírì.*+ 42 Nóbà lọ gbógun ja Kénátì, ó sì gbà á, tòun ti àwọn àrọko rẹ̀,* ó wá ń fi Nóbà orúkọ ara rẹ̀ pè é.
33 Bí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe rìnrìn àjò wọn ní àwùjọ-àwùjọ*+ nìyí láti ibì kan sí ibòmíì nígbà tí wọ́n kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì,+ tí Mósè àti Áárónì+ sì ń darí wọn. 2 Bí wọ́n ṣe ń lọ láti ibì kan sí ibòmíì lẹ́nu ìrìn àjò wọn ni Mósè ń kọ àwọn ibi tí wọ́n ti ń gbéra sílẹ̀, bí Jèhófà ṣe pa á láṣẹ. Bí wọ́n ṣe gbéra láti ibì kan sí ibòmíì+ nìyí: 3 Wọ́n kúrò ní Rámésésì+ ní ọjọ́ kẹẹ̀ẹ́dógún oṣù+ kìíní. Ọjọ́ tó tẹ̀ lé Ìrékọjá+ gangan ni àwọn ọmọ Ísírẹ́lì fi ìgboyà* jáde níṣojú gbogbo àwọn ará Íjíbítì. 4 Ìgbà yẹn ni àwọn ará Íjíbítì ń sin àwọn àkọ́bí wọn+ tí Jèhófà pa torí Jèhófà ti dá àwọn ọlọ́run+ wọn lẹ́jọ́.
5 Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kúrò ní Rámésésì, wọ́n sì pàgọ́ sí Súkótù.+ 6 Lẹ́yìn náà, wọ́n kúrò ní Súkótù, wọ́n sì pàgọ́ sí Étámù+ tó wà létí aginjù. 7 Wọ́n tún kúrò ní Étámù, wọ́n sì ṣẹ́rí pa dà gba Píháhírótì, níbi tí wọ́n á ti máa wo Baali-séfónì+ lọ́ọ̀ọ́kán, wọ́n sì pàgọ́ síwájú Mígídólì.+ 8 Lẹ́yìn náà, wọ́n kúrò ní Píháhírótì, wọ́n sì gba àárín òkun+ kọjá lọ sí aginjù, wọ́n wá rin ìrìn ọjọ́ mẹ́ta ní aginjù+ Étámù,+ wọ́n sì pàgọ́ sí Márà.+
9 Lẹ́yìn náà, wọ́n kúrò ní Márà, wọ́n sì lọ sí Élímù. Ìsun omi méjìlá (12) àti àádọ́rin (70) igi ọ̀pẹ wà ní Élímù, wọ́n sì pàgọ́ síbẹ̀.+ 10 Wọ́n wá kúrò ní Élímù, wọ́n sì pàgọ́ sẹ́gbẹ̀ẹ́ Òkun Pupa. 11 Lẹ́yìn náà, wọ́n kúrò ní Òkun Pupa, wọ́n sì pàgọ́ sí aginjù Sínì.+ 12 Wọ́n kúrò ní aginjù Sínì, wọ́n sì pàgọ́ sí Dófíkà. 13 Lẹ́yìn náà, wọ́n kúrò ní Dófíkà, wọ́n sì pàgọ́ sí Álúṣì. 14 Wọ́n wá kúrò ní Álúṣì, wọ́n sì pàgọ́ sí Réfídímù,+ níbi tí àwọn èèyàn náà ò ti rí omi mu. 15 Lẹ́yìn tí wọ́n kúrò ní Réfídímù, wọ́n pàgọ́ sí aginjù Sínáì.+
16 Wọ́n kúrò ní aginjù Sínáì, wọ́n sì pàgọ́ sí Kiburoti-hátááfà.+ 17 Wọ́n wá kúrò ní Kiburoti-hátááfà, wọ́n sì pàgọ́ sí Hásérótì.+ 18 Lẹ́yìn náà, wọ́n kúrò ní Hásérótì, wọ́n sì pàgọ́ sí Rítímà. 19 Lẹ́yìn náà, wọ́n kúrò ní Rítímà, wọ́n sì pàgọ́ sí Rimoni-pérésì. 20 Wọ́n wá kúrò ní Rimoni-pérésì, wọ́n sì pàgọ́ sí Líbínà. 21 Wọ́n kúrò ní Líbínà, wọ́n sì pàgọ́ sí Rísà. 22 Lẹ́yìn tí wọ́n kúrò ní Rísà, wọ́n pàgọ́ sí Kéhélátà. 23 Wọ́n wá kúrò ní Kéhélátà, wọ́n sì pàgọ́ sí Òkè Ṣéférì.
24 Lẹ́yìn náà, wọ́n kúrò ní Òkè Ṣéférì, wọ́n sì pàgọ́ sí Hárádà. 25 Wọ́n wá kúrò ní Hárádà, wọ́n sì pàgọ́ sí Mákélótì. 26 Lẹ́yìn tí wọ́n kúrò+ ní Mákélótì, wọ́n pàgọ́ sí Táhátì. 27 Wọ́n wá kúrò ní Táhátì, wọ́n sì pàgọ́ sí Térà. 28 Lẹ́yìn náà, wọ́n kúrò ní Térà, wọ́n sì pàgọ́ sí Mítíkà. 29 Wọ́n wá kúrò ní Mítíkà, wọ́n sì pàgọ́ sí Háṣímónà. 30 Lẹ́yìn tí wọ́n kúrò ní Háṣímónà, wọ́n pàgọ́ sí Mósérótì. 31 Wọ́n wá kúrò ní Mósérótì, wọ́n sì pàgọ́ sí Bẹne-jáákánì.+ 32 Lẹ́yìn náà, wọ́n kúrò ní Bẹne-jáákánì, wọ́n sì pàgọ́ sí Hoori-hágígádì. 33 Wọ́n wá kúrò ní Hoori-hágígádì, wọ́n sì pàgọ́ sí Jótíbátà.+ 34 Lẹ́yìn tí wọ́n kúrò ní Jótíbátà, wọ́n pàgọ́ sí Ábúrónà. 35 Wọ́n wá kúrò ní Ábúrónà, wọ́n sì pàgọ́ sí Esioni-gébérì.+ 36 Lẹ́yìn tí wọ́n kúrò ní Esioni-gébérì, wọ́n pàgọ́ sí aginjù Síínì,+ ìyẹn Kádéṣì.
37 Wọ́n wá kúrò ní Kádéṣì, wọ́n sì pàgọ́ sí Òkè Hóórì,+ ní ààlà ilẹ̀ Édómù. 38 Àlùfáà Áárónì wá gun Òkè Hóórì lọ bí Jèhófà ṣe pa á láṣẹ, ó sì kú síbẹ̀ ní ọjọ́ kìíní, oṣù+ karùn-ún, ọdún ogójì tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì. 39 Ẹni ọdún mẹ́tàlélọ́gọ́fà (123) ni Áárónì nígbà tó kú lórí Òkè Hóórì.
40 Ó ṣẹlẹ̀ pé ọba Árádì,+ ọmọ Kénáánì tó ń gbé ní Négébù, ní ilẹ̀ Kénáánì gbọ́ pé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ti ń bọ̀.
41 Nígbà tó yá, wọ́n kúrò ní Òkè Hóórì,+ wọ́n sì pàgọ́ sí Sálímónà. 42 Lẹ́yìn náà, wọ́n kúrò ní Sálímónà, wọ́n sì pàgọ́ sí Púnónì. 43 Wọ́n wá kúrò ní Púnónì, wọ́n sì pàgọ́ sí Óbótì.+ 44 Lẹ́yìn náà, wọ́n kúrò ní Óbótì, wọ́n sì pàgọ́ sí Iye-ábárímù ní ààlà Móábù.+ 45 Wọ́n wá kúrò ní Íyímù, wọ́n sì pàgọ́ sí Diboni-gádì.+ 46 Lẹ́yìn náà, wọ́n kúrò ní Diboni-gádì, wọ́n sì pàgọ́ sí Alimoni-díbílátáímù. 47 Wọ́n wá kúrò ní Alimoni-díbílátáímù, wọ́n sì pàgọ́ sí àwọn òkè Ábárímù+ níwájú Nébò.+ 48 Níkẹyìn, wọ́n kúrò ní àwọn òkè Ábárímù, wọ́n sì pàgọ́ sí aṣálẹ̀ tó tẹ́jú ní Móábù, lẹ́gbẹ̀ẹ́ Jọ́dánì ní Jẹ́ríkò.+ 49 Wọ́n wá ń pàgọ́ sẹ́gbẹ̀ẹ́ Jọ́dánì láti Bẹti-jẹ́ṣímótì títí lọ dé Ebẹli-ṣítímù,+ ní aṣálẹ̀ tó tẹ́jú ní Móábù.
50 Jèhófà sọ fún Mósè ní aṣálẹ̀ tó tẹ́jú ní Móábù, lẹ́gbẹ̀ẹ́ Jọ́dánì ní Jẹ́ríkò pé: 51 “Sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé, ‘Ẹ máa sọdá Jọ́dánì sí ilẹ̀ Kénáánì.+ 52 Kí ẹ lé gbogbo àwọn tó ń gbé ilẹ̀ náà kúrò níwájú yín, kí ẹ run gbogbo ère tí wọ́n fi òkúta+ ṣe àti gbogbo ère onírin*+ wọn, kí ẹ sì wó gbogbo ibi gíga+ tí wọ́n ti ń jọ́sìn àwọn òrìṣà. 53 Ẹ ó gba ilẹ̀ náà, ẹ ó sì máa gbé níbẹ̀, torí ó dájú pé màá fún yín ní ilẹ̀ náà kó lè di tiyín.+ 54 Kí ẹ fi kèké+ pín ilẹ̀ náà bí ohun ìní láàárín àwọn ìdílé yín. Kí ẹ fi kún ogún tí ẹ máa pín fún àwùjọ tó bá pọ̀, kí ẹ sì dín ogún+ tí ẹ máa pín fún àwùjọ tó bá kéré kù. Ibi tí kèké kálukú bá bọ́ sí ni ohun ìní rẹ̀ máa wà. Ẹ̀yà àwọn bàbá+ yín la máa fi pín ogún fún yín.
55 “‘Àmọ́ tí ẹ ò bá lé àwọn tó ń gbé ilẹ̀ náà kúrò níwájú yín,+ àwọn tí ẹ bá fi sílẹ̀ lára wọn máa dà bí ohun ìríra lójú yín, wọ́n á dà bí ẹ̀gún tó ń gún yín lẹ́gbẹ̀ẹ́, wọ́n á sì máa yọ yín lẹ́nu ní ilẹ̀ tí ẹ máa gbé.+ 56 Ohun tí mo sì fẹ́ ṣe sí wọn ni màá ṣe sí yín.’”+
34 Jèhófà ń bá ọ̀rọ̀ tó ń sọ fún Mósè lọ pé: 2 “Fi ìtọ́ni yìí tó àwọn ọmọ Ísírẹ́lì létí pé, ‘Tí ẹ bá wọ ilẹ̀ Kénáánì,+ ilẹ̀ tó máa di tiyín nìyí láwọn ibi tí ààlà+ rẹ̀ dé.
3 “‘Kí ààlà gúúsù yín bẹ̀rẹ̀ láti aginjù Síínì lẹ́gbẹ̀ẹ́ Édómù, kí ààlà gúúsù yín lápá ìlà oòrùn sì jẹ́ láti ìkángun Òkun Iyọ̀.*+ 4 Kí ààlà yín sì yí gba gúúsù, kó gba ibi tí wọ́n ń gbà gòkè ní Ákírábímù+ títí lọ dé Síínì, kó sì parí sí gúúsù Kadeṣi-báníà.+ Kó wá dé Hasari-ádáárì+ títí lọ dé Ásímónì. 5 Kí ààlà náà yí gba Àfonífojì Íjíbítì láti Ásímónì, kó sì parí sí Òkun.*+
6 “‘Ààlà yín ní ìwọ̀ oòrùn máa jẹ́ Òkun Ńlá* àti èbúté. Èyí ni yóò jẹ́ ààlà yín ní ìwọ̀ oòrùn.+
7 “‘Èyí ni yóò jẹ́ ààlà yín ní àríwá: Kí ẹ pààlà yín láti Òkun Ńlá dé Òkè Hóórì. 8 Kí ẹ pààlà yín láti Òkè Hóórì dé Lebo-hámátì,*+ kí ààlà náà sì parí sí Sédádì.+ 9 Kí ààlà náà lọ títí dé Sífírónì, kó sì parí sí Hasari-énánì.+ Èyí ni yóò jẹ́ ààlà yín ní àríwá.
10 “‘Ní ìlà oòrùn, kí ẹ pààlà yín láti Hasari-énánì dé Ṣẹ́fámù. 11 Kí ààlà náà lọ láti Ṣẹ́fámù dé Ríbúlà ní ìlà oòrùn Áyínì, kí ààlà náà sì gba ìsàlẹ̀ lọ kan gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ ìlà oòrùn Òkun Kínérétì.*+ 12 Kí ààlà náà lọ dé Jọ́dánì, kó sì parí sí Òkun Iyọ̀.+ Èyí ni yóò jẹ́ ilẹ̀+ yín àti àwọn ààlà rẹ̀ yí ká.’”
13 Mósè wá sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé: “Èyí ni ilẹ̀ tí ẹ máa fi kèké+ pín bí ohun ìní, bí Jèhófà ṣe pa á láṣẹ gẹ́lẹ́ pé kí wọ́n fún ẹ̀yà mẹ́sàn-án àti ààbọ̀. 14 Torí pé ẹ̀yà àwọn ọmọ Rúbẹ́nì gẹ́gẹ́ bí agbo ilé bàbá wọn, àwọn ọmọ Gádì gẹ́gẹ́ bí agbo ilé bàbá wọn àti ààbọ̀ ẹ̀yà Mánásè ti gba ogún+ tiwọn. 15 Ẹ̀yà méjì ààbọ̀ ti gba ogún tiwọn ní ìlà oòrùn agbègbè Jọ́dánì lẹ́gbẹ̀ẹ́ Jẹ́ríkò, lápá ibi tí oòrùn ti ń yọ.”+
16 Jèhófà ń bá ọ̀rọ̀ tó ń sọ fún Mósè lọ pé: 17 Orúkọ àwọn ọkùnrin tó máa pín ilẹ̀ tí yóò di tiyín fún yín nìyí: àlùfáà Élíásárì+ àti Jóṣúà+ ọmọ Núnì. 18 Kí ẹ mú ìjòyè kan látinú ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan tó máa pín ilẹ̀ tí ẹ máa jogún+ fún yín. 19 Orúkọ àwọn ọkùnrin náà nìyí: látinú ẹ̀yà Júdà,+ Kélẹ́bù+ ọmọ Jéfúnè; 20 látinú ẹ̀yà àwọn ọmọ Síméónì,+ Ṣẹ́múẹ́lì ọmọ Ámíhúdù; 21 látinú ẹ̀yà Bẹ́ńjámínì,+ Élídádì ọmọ Kísílónì; 22 látinú ẹ̀yà àwọn ọmọ Dánì,+ ìjòyè kan, Búkì ọmọ Jógílì; 23 látinú ẹ̀yà àwọn ọmọ Jósẹ́fù,+ láti ẹ̀yà àwọn ọmọ Mánásè,+ ìjòyè kan, Háníélì ọmọ Éfódì; 24 látinú ẹ̀yà àwọn ọmọ Éfúrémù,+ ìjòyè kan, Kémúélì ọmọ Ṣífútánì; 25 látinú ẹ̀yà àwọn ọmọ Sébúlúnì,+ ìjòyè kan, Élísáfánì ọmọ Pánákì; 26 látinú ẹ̀yà àwọn ọmọ Ísákà,+ ìjòyè kan, Pálítíélì ọmọ Ásánì; 27 látinú ẹ̀yà àwọn ọmọ Áṣérì,+ ìjòyè kan, Áhíhúdù ọmọ Ṣẹ́lómì; 28 látinú ẹ̀yà àwọn ọmọ Náfútálì,+ ìjòyè kan, Pédáhélì ọmọ Ámíhúdù.” 29 Àwọn yìí ni Jèhófà pàṣẹ pé kí wọ́n pín ilẹ̀ náà fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní ilẹ̀ Kénáánì.+
35 Jèhófà sọ fún Mósè ní aṣálẹ̀ tó tẹ́jú ní Móábù, lẹ́gbẹ̀ẹ́ Jọ́dánì+ ní Jẹ́ríkò pé: 2 “Sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé kí wọ́n fún àwọn ọmọ Léfì ní àwọn ìlú tí wọ́n á máa gbé látinú ogún tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì máa gbà,+ kí wọ́n sì fún àwọn ọmọ Léfì ní àwọn ibi ìjẹko tó yí àwọn ìlú+ náà ká. 3 Wọ́n á máa gbé àwọn ìlú náà, ibi ìjẹko náà á sì wà fún àwọn ẹran ọ̀sìn wọn, àwọn ẹrù wọn àti gbogbo ẹran wọn yòókù. 4 Kí ibi ìjẹko tó yí àwọn ìlú tí ẹ máa fún àwọn ọmọ Léfì ká jẹ́ ẹgbẹ̀rún (1,000) ìgbọ̀nwọ́* láti ògiri ìlú náà yí ká. 5 Ní ẹ̀yìn ìlú náà, kí ẹ wọn ẹgbẹ̀rún méjì (2,000) ìgbọ̀nwọ́ ní apá ìlà oòrùn, ẹgbẹ̀rún méjì (2,000) ìgbọ̀nwọ́ ní apá gúúsù, ẹgbẹ̀rún méjì (2,000) ìgbọ̀nwọ́ ní apá ìwọ̀ oòrùn àti ẹgbẹ̀rún méjì (2,000) ìgbọ̀nwọ́ ní apá àríwá, kí ìlú náà wà ní àárín. Ìwọ̀nyí ló máa jẹ́ ibi ìjẹko àwọn ìlú náà.
6 “Ìlú mẹ́fà ni kí ẹ fún àwọn ọmọ Léfì láti fi ṣe ìlú ààbò,+ tí ẹ máa ní kí apààyàn sá lọ,+ kí ẹ sì tún fún wọn ní ìlú méjìlélógójì (42) míì. 7 Kí àpapọ̀ àwọn ìlú tí ẹ máa fún àwọn ọmọ Léfì jẹ́ méjìdínláàádọ́ta (48), pẹ̀lú àwọn ibi ìjẹko+ wọn. 8 Látinú ohun ìní àwọn ọmọ Ísírẹ́lì+ ni kí ẹ ti fún wọn ní àwọn ìlú náà. Kí ẹ gba púpọ̀ lọ́wọ́ àwùjọ tó pọ̀, kí ẹ sì gba díẹ̀+ lọ́wọ́ àwùjọ tó kéré. Kí àwùjọ kọ̀ọ̀kan fún àwọn ọmọ Léfì lára àwọn ìlú rẹ̀ bí ogún tó gbà bá ṣe pọ̀ tó.”
9 Jèhófà ń bá ọ̀rọ̀ tó ń sọ fún Mósè lọ pé: 10 “Sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé, ‘Ẹ máa sọdá Jọ́dánì sí ilẹ̀ Kénáánì.+ 11 Kí ẹ yan àwọn ìlú tó rọ̀ yín lọ́rùn láti fi ṣe ìlú ààbò, tí ẹni* tó bá ṣèèṣì pa èèyàn* máa sá lọ.+ 12 Kí àwọn ìlú yìí jẹ́ ìlú ààbò fún yín lọ́wọ́ ẹni tó ń gbẹ̀san ẹ̀jẹ̀,+ kí apààyàn náà má bàa kú kí wọ́n tó gbọ́ ẹjọ́ rẹ̀ níwájú àpéjọ+ náà. 13 Ohun tí àwọn ìlú mẹ́fẹ̀ẹ̀fà tí ẹ yàn pé kó jẹ́ ibi ààbò máa wà fún nìyẹn. 14 Kí ẹ yan ìlú mẹ́ta ní apá ibí yìí ní Jọ́dánì,+ kí ẹ sì yan ìlú mẹ́ta ní ilẹ̀ Kénáánì+ láti fi ṣe ìlú ààbò. 15 Ìlú mẹ́fà yìí máa jẹ́ ìlú ààbò fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, àwọn àjèjì+ àtàwọn tí wọ́n jọ ń gbé, ibẹ̀ ni ẹnikẹ́ni tó bá ṣèèṣì pa èèyàn*+ máa sá wọ̀.
16 “‘Àmọ́ tó bá jẹ́ ohun tí wọ́n fi irin ṣe ni ẹnì kan fi lu ẹnì kejì rẹ̀, tó sì kú, apààyàn ni. Ẹ gbọ́dọ̀ pa apààyàn náà.+ 17 Tó bá jẹ́ òkúta tó lè pààyàn ló sọ lu ẹni náà, tó sì kú, apààyàn ni. Ẹ gbọ́dọ̀ pa apààyàn náà. 18 Tó bá sì jẹ́ ohun tí wọ́n fi igi ṣe tó lè pààyàn ló fi lù ú, tó sì kú, apààyàn ni. Ẹ gbọ́dọ̀ pa apààyàn náà.
19 “‘Ẹni tó ń gbẹ̀san ẹ̀jẹ̀ ló máa pa apààyàn náà. Tó bá ti ṣe kòńgẹ́ rẹ̀, òun fúnra rẹ̀ ló máa pa á. 20 Tí ẹnì kan bá kórìíra ẹnì kejì rẹ̀, tó sì tì í tàbí tó ń gbèrò ibi+ sí i,* tó sì ju nǹkan lù ú, tí ẹni náà wá kú, 21 tàbí tó kórìíra ẹnì kejì rẹ̀, tó sì fi ọwọ́ lù ú, tí ẹni náà wá kú, ṣe ni kí ẹ pa ẹni tó lu ẹnì kejì rẹ̀ pa. Apààyàn ni. Ẹni tó ń gbẹ̀san ẹ̀jẹ̀ máa pa apààyàn náà tó bá ti ṣe kòńgẹ́ rẹ̀.
22 “‘Àmọ́ tó bá jẹ́ pé ńṣe ló ṣèèṣì tì í, tí kì í ṣe pé ó kórìíra rẹ̀ tàbí tó ju nǹkan lù ú láì gbèrò ibi+ sí i,* 23 tàbí tó ṣèèṣì sọ òkúta lù ú láìmọ̀ pé ó wà níbẹ̀, tí kì í sì í ṣe pé ọ̀tá rẹ̀ ni tàbí pé ó fẹ́ ṣe é léṣe, tí ẹni náà sì kú, 24 kí àpéjọ náà tẹ̀ lé ìdájọ́+ wọ̀nyí láti dá ẹjọ́ ẹni tó pààyàn àti ẹni tó ń gbẹ̀san ẹ̀jẹ̀. 25 Kí àpéjọ náà wá gba apààyàn náà sílẹ̀ lọ́wọ́ ẹni tó ń gbẹ̀san ẹ̀jẹ̀, kí wọ́n sì dá a pa dà sí ìlú ààbò rẹ̀ tó sá lọ, kó sì máa gbé níbẹ̀ títí ọjọ́ tí àlùfáà àgbà tí wọ́n fi òróró mímọ́+ yàn fi máa kú.
26 “‘Àmọ́ tí apààyàn náà bá kọjá ààlà ìlú ààbò rẹ̀ tó sá wọ̀, 27 tí ẹni tó ń gbẹ̀san ẹ̀jẹ̀ sì rí i lẹ́yìn ààlà ìlú ààbò rẹ̀, tó sì pa á, kò jẹ̀bi ẹ̀jẹ̀. 28 Torí ìlú ààbò rẹ̀ ló gbọ́dọ̀ máa gbé títí àlùfáà àgbà fi máa kú. Àmọ́ tí àlùfáà àgbà bá ti kú, apààyàn náà lè pa dà sí ilẹ̀ rẹ̀.+ 29 Kí ìwọ̀nyí jẹ́ àṣẹ tí ẹ ó máa tẹ̀ lé láti ṣe ìdájọ́ jálẹ̀ àwọn ìran yín ní gbogbo ibi tí ẹ̀ ń gbé.
30 “‘Kí ẹ tó pa ẹnikẹ́ni tó bá pa èèyàn,* àwọn èèyàn gbọ́dọ̀ jẹ́rìí sí i* pé apààyàn+ ni; àmọ́ ẹ má pa ẹnikẹ́ni* tó bá jẹ́ pé ẹnì kan péré ló jẹ́rìí+ sí i. 31 Ẹ ò gbọ́dọ̀ gba ìràpadà fún ẹ̀mí* apààyàn tí ikú tọ́ sí, ṣe ni kí ẹ pa á.+ 32 Ẹ ò sì gbọ́dọ̀ gba ìràpadà fún ẹnì kan tó sá lọ sí ìlú ààbò rẹ̀ pé kó wá máa gbé ní ilẹ̀ rẹ̀ nígbà tí àlùfáà àgbà ò tíì kú.
33 “‘Ẹ má sọ ilẹ̀ tí ẹ̀ ń gbé di ẹlẹ́gbin, torí ẹ̀jẹ̀ máa ń sọ ilẹ̀+ di ẹlẹ́gbin, kò sì sí ètùtù fún ẹ̀jẹ̀ tí ẹnì kan ta sórí ilẹ̀ àyàfi ẹ̀jẹ̀ ẹni náà tó ta á sílẹ̀.+ 34 Ẹ má sọ ilẹ̀ tí ẹ̀ ń gbé di aláìmọ́, ilẹ̀ tí mò ń gbé; torí èmi Jèhófà ń gbé láàárín àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.’”+
36 Àwọn olórí ìdílé àwọn àtọmọdọ́mọ Gílíádì ọmọ Mákírù+ ọmọ Mánásè láti ìdílé àwọn ọmọ Jósẹ́fù wá sọ́dọ̀ Mósè àti àwọn ìjòyè, àwọn olórí ìdílé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, láti bá wọn sọ̀rọ̀. 2 Wọ́n sọ pé: “Jèhófà pàṣẹ fún olúwa mi pé kó fi kèké+ pín ilẹ̀ náà fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kí wọ́n lè jogún rẹ̀; Jèhófà sì pàṣẹ fún olúwa mi pé kó fún àwọn ọmọbìnrin + Sélóféhádì arákùnrin wa ní ogún bàbá wọn. 3 Àmọ́ tí wọ́n bá lọ́kọ látinú ẹ̀yà míì ní Ísírẹ́lì, ogún àwọn obìnrin náà máa kúrò nínú ogún àwọn bàbá wa, ó sì máa kún ti ogún ẹ̀yà tí wọ́n máa fẹ́ wọn sí, kò wá ní sí lára ogún tí wọ́n fi kèké pín fún wa. 4 Tí àkókò Júbílì+ bá wá tó fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, ogún àwọn obìnrin náà máa kún ti ogún ẹ̀yà tí wọ́n máa fẹ́ wọn sí, ogún wọn ò sì ní sí lára ogún ẹ̀yà àwọn bàbá wa mọ́.”
5 Mósè wá pàṣẹ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì bí Jèhófà ṣe pa á láṣẹ pé: “Òótọ́ ni ohun tí ẹ̀yà àwọn ọmọ Jósẹ́fù ń sọ. 6 Ohun tí Jèhófà sọ nípa àwọn ọmọbìnrin Sélóféhádì ni pé: ‘Wọ́n lè fẹ́ ẹni tó bá wù wọ́n. Àmọ́, inú ìdílé tó wá látinú ẹ̀yà bàbá wọn ni kí wọ́n ti fẹ́ ẹ. 7 Ogún èyíkéyìí tó jẹ́ ti àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kò gbọ́dọ̀ ti ọwọ́ ẹ̀yà kan bọ́ sí òmíràn, torí kò yẹ kí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì fi ogún ẹ̀yà baba ńlá wọn sílẹ̀. 8 Kí ọmọbìnrin èyíkéyìí tó bá ní ogún láàárín ẹ̀yà àwọn ọmọ Ísírẹ́lì fẹ́ ọ̀kan nínú àtọmọdọ́mọ ẹ̀yà+ bàbá rẹ̀, kí ogún baba ńlá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lè máa wà ní ìkáwọ́ wọn. 9 Ogún èyíkéyìí kò gbọ́dọ̀ ti ọwọ́ ẹ̀yà kan bọ́ sí òmíràn, torí kò yẹ kí àwọn ẹ̀yà Ísírẹ́lì fi ogún wọn sílẹ̀.’”
10 Àwọn ọmọbìnrin Sélóféhádì ṣe ohun tí Jèhófà pa láṣẹ fún Mósè+ gẹ́lẹ́. 11 Torí náà, Málà, Tírísà, Hógílà, Mílíkà àti Nóà, àwọn ọmọbìnrin Sélóféhádì,+ fẹ́ ọkọ láàárín àwọn ọmọ àwọn arákùnrin bàbá wọn. 12 Wọ́n lọ́kọ nínú ìdílé Mánásè ọmọ Jósẹ́fù, kí ogún wọn má bàa kúrò nínú ẹ̀yà ìdílé bàbá wọn.
13 Èyí ni àwọn àṣẹ àti àwọn ìlànà ìdájọ́ tí Jèhófà fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nípasẹ̀ Mósè ní aṣálẹ̀ tó tẹ́jú ní Móábù, lẹ́gbẹ̀ẹ́ Jọ́dánì ní Jẹ́ríkò.+
Ní Héb., “àwọn ọmọkùnrin Ísírẹ́lì.”
Tàbí “ní orí ò jorí.”
Ní Héb., “ẹgbẹ́ ọmọ ogun kọ̀ọ̀kan.”
Ní Héb., “àjèjì kankan,” ìyẹn ẹni tí kì í ṣe ọmọ Léfì.
Tàbí “tí àmì (àkọlé) rẹ̀ wà.”
Ní Héb., “ẹgbẹ́ ọmọ ogun kọ̀ọ̀kan.”
Tàbí “ṣọ́; ṣiṣẹ́ ní.”
Tàbí “àmì.”
Ní Héb., “ẹgbẹ́ ọmọ ogun kọ̀ọ̀kan.”
Ní Héb., “ẹgbẹ́ ọmọ ogun kọ̀ọ̀kan.”
Ní Héb., “ẹgbẹ́ ọmọ ogun kọ̀ọ̀kan.”
Ní Héb., “ẹgbẹ́ ọmọ ogun kọ̀ọ̀kan.”
Ní Héb., “ìran.”
Ní Héb., “tí wọ́n fi kún ọwọ́ wọn.”
Ní Héb., “àjèjì kankan,” ìyẹn ẹni tí kì í ṣe ara ìdílé Áárónì.
Ní Héb., “gbogbo àkọ́bí tó ṣí ilé ọmọ.”
Tàbí “aṣọ àgọ́.”
Tàbí “aṣọ ìdábùú.”
Tàbí “aṣọ ìdábùú.”
Tàbí “aṣọ ìdábùú.”
Ní Héb., “àjèjì kankan,” ìyẹn ẹni tí kì í ṣe ọmọ Léfì.
Ṣékélì kan jẹ́ gíráàmù 11.4. Wo Àfikún B14.
Tàbí “ṣékélì mímọ́.”
Gérà kan jẹ́ gíráàmù 0.57. Wo Àfikún B14.
Ní Héb., “ẹnu.”
Ní Héb., “ibùdó.”
Tàbí “ẹ̀mú.”
Tàbí “eérú ọlọ́ràá,” ìyẹn, eérú tí ọ̀rá tí wọ́n fi rúbọ ti rin.
Ní Héb., “ibùdó.”
Ní Héb., “Ẹrù.”
Tàbí “aṣọ ìdábùú.”
Tàbí “aṣọ ìdábùú.”
Tàbí “ẹni tí ọkàn.” Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.
Tàbí “pàgọ́ sáàárín wọn.”
Tàbí “ọkàn.”
Ní Héb., “Wọ́n.”
Tàbí “tí wọ́n.”
Ìdá mẹ́wàá òṣùwọ̀n eéfà kan jẹ́ Lítà 2.2. Wo Àfikún B14.
Ó ṣe kedere pé ẹ̀yà ìbímọ ló ń tọ́ka sí.
Tàbí “tín-ín-rín.” Ó ṣeé ṣe kó túmọ̀ sí pé kò ní rọ́mọ bí.
Ó ṣe kedere pé ẹ̀yà ìbímọ ló ń tọ́ka sí.
Tàbí “tín-ín-rín.” Ó ṣeé ṣe kó túmọ̀ sí pé kò ní rọ́mọ bí.
Tàbí “Bẹ́ẹ̀ ni kó rí! Bẹ́ẹ̀ ni kó rí!”
Ó ṣe kedere pé ẹ̀yà ìbímọ ló ń tọ́ka sí.
Tàbí “tín-ín-rín.” Ó ṣeé ṣe kó túmọ̀ sí pé kò ní rọ́mọ bí.
Lédè Hébérù, na·zirʹ, ó túmọ̀ sí “Ẹni Tí A Yàn; Ẹni Tí A Yà Sí Mímọ́; Ẹni Tí A Yà Sọ́tọ̀.”
Tàbí “wá sí tòsí.”
Tàbí “ọkàn.” Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.
Tàbí “sọ orí Násírì rẹ̀ di aláìmọ́.”
Tàbí “ọkàn.” Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.
Tàbí “orí Násírì rẹ̀.”
Tàbí “màlúù.”
Tàbí “ayẹyẹ tí wọ́n fi máa ṣí.”
Ṣékélì kan jẹ́ gíráàmù 11.4. Wo Àfikún B14.
Tàbí “ṣékélì mímọ́.”
Tàbí “abọ́ kékeré.”
Ní Héb., “bá a.”
Ní Héb., “fi àwọn ọmọ Léfì,” ìyẹn ni pé, kó fì wọ́n síwá-sẹ́yìn.
Ní Héb., “fì wọ́n,” ìyẹn ni pé, kó fì wọ́n síwá-sẹ́yìn.
Ní Héb., “fì wọ́n,” ìyẹn ni pé, kó fì wọ́n síwá-sẹ́yìn.
Tàbí “gbogbo àkọ́bí tó ṣí ilé ọmọ.”
Ní Héb., “fì wọ́n,” ìyẹn ni pé, kó fì wọ́n síwá-sẹ́yìn.
Ní Héb., “Láàárín ìrọ̀lẹ́ méjèèjì.”
Ní Héb., “Láàárín ìrọ̀lẹ́ méjèèjì.”
Tàbí “ọkàn kan.”
Tàbí “torí ọkàn kan.”
Tàbí “ọkàn kan.”
Ní Héb., “láàárín ìrọ̀lẹ́ méjèèjì.”
Tàbí “ọkàn.”
Tàbí “àwọsánmà.”
Tàbí “àwọsánmà.”
Ní Héb., “ẹgbẹ́ ọmọ ogun kọ̀ọ̀kan.”
Ní Héb., “ẹgbẹ́ ọmọ ogun kọ̀ọ̀kan.”
Ní Héb., “ẹgbẹ́ ọmọ ogun kọ̀ọ̀kan.”
Ní Héb., “ẹgbẹ́ ọmọ ogun kọ̀ọ̀kan.”
Ní Héb., “ẹgbẹ́ ọmọ ogun kọ̀ọ̀kan.”
Ìyẹn, Jẹ́tírò.
Tàbí “ṣe bí ojú fún wa.”
Tàbí “ọ̀kẹ́ àìmọye.”
Ó túmọ̀ sí “Ó Ń Jó,” ìyẹn iná ajónirun; iná tó ń jó lala.
Ó jọ pé àwọn tí kì í ṣe ọmọ Ísírẹ́lì tó wà láàárín wọn ló ń sọ.
Tàbí “apálá.”
Tàbí “ọkàn wa.”
Tàbí “olùtọ́jú tó jẹ́ ọkùnrin.”
Tàbí “àwọn tí o mọ̀ sí.”
Ní Héb., “àwọn ọkùnrin tó ń fẹsẹ̀ rìn,” ìyẹn, àwọn ọkùnrin tó lè jagun.
Tàbí “àwọsánmà.”
Tàbí “wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í sọ tẹ́lẹ̀.”
Ìgbọ̀nwọ́ kan jẹ́ sẹ̀ǹtímítà 44.5 (ínǹṣì 17.5). Wo Àfikún B14.
Hómérì kan jẹ́ òṣùwọ̀n tó gba Lítà 220. Wo Àfikún B14.
Ó túmọ̀ sí “Ibi Ìsìnkú Àwọn Tó Ní Ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́.”
Tàbí “lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀ (jẹ́ oníwà tútù) ju gbogbo èèyàn.”
Tàbí “àwọsánmà tó rí bí òpó.”
Ní Héb., “Ó ń fi hàn pé òun jẹ́ olóòótọ́ nínú gbogbo ilé mi.”
Ní Héb., “Ẹnu ko ẹnu.”
Tàbí “ṣàyẹ̀wò.”
Tàbí “Jèhóṣúà,” ó túmọ̀ sí “Jèhófà Ni Ìgbàlà.”
Ní Héb., “lọ́ràá.”
Ní Héb., “kò lọ́ràá.”
Tàbí “àbáwọlé Hámátì.”
Ó túmọ̀ sí “Òṣùṣù Èso Àjàrà.”
Tàbí “wá láti ara.”
Ní Héb., “oúnjẹ ni wọ́n jẹ́ fún wa.”
Tàbí “àwọsánmà tó rí bí òpó.”
Tàbí “iná tó rí bí òpó.”
Ní Héb., “bí ẹnì kan ṣoṣo.”
Tàbí “inú rere onífẹ̀ẹ́ rẹ̀.”
Tàbí “pẹ̀tẹ́lẹ̀.”
Ní Héb., “tí mo gbé ọwọ́ mi sókè.”
Ní Héb., “iṣẹ́ aṣẹ́wó tí ẹ ṣe.”
Tàbí “láti jẹ́ ọ̀tá mi.”
Lédè Hébérù, ó tún túmọ̀ sí “ìgbójú” tàbí “ìkọjá àyè.”
Tàbí “tó tuni lójú.” Ní Héb., “atura.”
Ìdá mẹ́wàá òṣùwọ̀n eéfà kan jẹ́ Lítà 2.2. Wo Àfikún B14.
Òṣùwọ̀n hínì kan jẹ́ Lítà 3.67. Wo Àfikún B14.
Tàbí “tó tuni lójú.” Ní Héb., “atura.”
Tàbí “tó tuni lójú.” Ní Héb., “atura.”
Tàbí “tó tuni lójú.” Ní Héb., “atura.”
Tàbí “tó tuni lójú.” Ní Héb., “atura.”
Tàbí “búrẹ́dì.”
Tàbí “tó tuni lójú.” Ní Héb., “atura.”
Tàbí “ọkàn èyíkéyìí.”
Tàbí “ọkàn.”
Tàbí “ọkàn.”
Tàbí “ọkàn.”
Tàbí “máa jẹ gàba.”
Ní Héb., “ẹ̀mí gbogbo ẹran ara.”
Tàbí “èrò ara mi.”
Ní Héb., “la ẹnu rẹ̀.”
Tàbí “Ṣìọ́ọ̀lù,” ìyẹn ibojì aráyé. Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.
Ní Héb., “la ẹnu rẹ̀.”
Tàbí “Ṣìọ́ọ̀lù,” ìyẹn ibojì aráyé. Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.
Ní Héb., “àjèjì kankan.”
Tàbí “àwọsánmà.”
Tàbí “rudi.”
Tàbí “rudi.”
Ní Héb., “àjèjì kankan,” ìyẹn ẹni tí kò wá láti ìdílé Áárónì.
Ní Héb., “àjèjì kankan,” ìyẹn ẹni tí kò wá láti ìdílé Áárónì.
Ìyẹn, gbogbo ohun tí wọ́n yà sí mímọ́ fún Ọlọ́run tí kò ṣeé gbà pa dà, tí kò sì ṣeé rà pa dà lọ́wọ́ Ọlọ́run.
Ní Héb., “ẹlẹ́ran ara.”
Ṣékélì kan jẹ́ gíráàmù 11.4. Wo Àfikún B14.
Tàbí “ṣékélì mímọ́.”
Gérà kan jẹ́ gíráàmù 0.57. Wo Àfikún B14.
Tàbí “tó tuni lójú.” Ní Héb., “atura.”
Ìyẹn, májẹ̀mú tó máa wà pẹ́ títí, tí kò sì ní yí pa dà.
Ní Héb., “ẹran ara rẹ̀.”
Ní Héb., “ẹran ara rẹ̀.”
Tàbí “òkú ọkàn èyíkéyìí.”
Ní Héb., “fi í.”
Tàbí “òkú, ọkàn ẹnikẹ́ni tó ti kú.” Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.
Tàbí “ọkàn.”
Tàbí “àwọn ọkàn.”
Tàbí “ọkàn.”
Tàbí “ọkàn.”
Ó túmọ̀ sí “Ìjà.”
Ní Héb., “ọ̀pọ̀ ọjọ́.”
Ní Héb., “ọwọ́ tó lágbára.”
Àkànlò èdè yìí ni wọ́n fi ń sọ pé èèyàn kú.
Ní Héb., “Áárónì máa kú síbẹ̀, wọ́n á sì sin ín bí àwọn èèyàn rẹ̀.”
Ó túmọ̀ sí “Ìparun Pátápátá.”
Tàbí “ọkàn àwọn èèyàn náà.”
Tàbí “ọkàn wa.”
Tàbí “kórìíra oúnjẹ játijàti yìí tẹ̀gbintẹ̀gbin.”
Tàbí “ejò oníná.”
Tàbí “ejò oníná.”
Ní Héb., “ẹnu.”
Tàbí “Ẹ dá a lóhùn.”
Ní Héb., “pápá.”
Tàbí kó jẹ́, “aṣálẹ̀, aginjù ”
Tàbí “ìlú tó yí i ká.”
Tàbí “ìlú tó yí i ká.”
Ó ṣe kedere pé Yúfírétì ni.
Ní Héb., “ojú ilẹ̀.”
Ní Héb., “ojú ilẹ̀.”
Ní Héb., “abo kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́.”
Tàbí “ó di kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀ ní gàárì.”
Ní Héb., “la ẹnu abo kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà.”
Tàbí “ọkàn mi.”
Tàbí “kábàámọ̀.”
Tàbí kó jẹ́, “aṣálẹ̀, aginjù.”
Ní Héb., “ó dáa ní ojú Jèhófà.”
Tàbí “àtọmọdọ́mọ.”
Ní Héb., “tó wà lọ́kàn mi.”
Tàbí “ní òpin àwọn ọjọ́.”
Tàbí “ẹ̀bátí orí Móábù.”
Tàbí “so ara rẹ̀ mọ́.”
Ní Héb., “orí.”
Ní Héb., “níwájú oòrùn.”
Tàbí “so ara wọn mọ́.”
Tàbí “aṣóró.”
Ní Héb., “la ẹnu rẹ̀.”
Tàbí “bí iye àwọn orúkọ náà bá ṣe pọ̀ tó.”
Àkànlò èdè yìí ni wọ́n fi ń sọ pé èèyàn kú.
Ní Héb., “ẹ̀mí gbogbo ẹran ara.”
Tàbí “iyì.”
Tàbí “tó tuni lójú.” Ní Héb., “atura.”
Ní Héb., “láàárín ìrọ̀lẹ́ méjèèjì.”
Ìdá mẹ́wàá òṣùwọ̀n eéfà kan jẹ́ Lítà 2.2. Wo Àfikún B14.
Òṣùwọ̀n hínì kan jẹ́ Lítà 3.67. Wo Àfikún B14.
Tàbí “tó tuni lójú.” Ní Héb., “atura.”
Ní Héb., “láàárín ìrọ̀lẹ́ méjèèjì.”
Tàbí “tó tuni lójú.” Ní Héb., “atura.”
Ní Héb., “àwọn oṣù yín.”
Tàbí “tó tuni lójú.” Ní Héb., “atura.”
Ní Héb., “búrẹ́dì.”
Tàbí “tó tuni lójú.” Ní Héb., “atura.”
Tàbí “tó tuni lójú.” Ní Héb., “atura.”
Tàbí “tó tuni lójú.” Ní Héb., “atura.”
Tàbí “tó tuni lójú.” Ní Héb., “atura.”
Tàbí “ọkàn yín.” Kí èèyàn “pọ́n ara rẹ̀ lójú” sábà máa ń túmọ̀ sí kí èèyàn fi oríṣiríṣi nǹkan du ara rẹ̀, irú bíi kó gbààwẹ̀.
Tàbí “tó tuni lójú.” Ní Héb., “atura.”
Tàbí “tó tuni lójú.” Ní Héb., “atura.”
Tàbí “tó tuni lójú.” Ní Héb., “atura.”
Tàbí “fi ohun kan de ọkàn òun láti.”
Tàbí “ọkàn òun.”
Tàbí “jẹ́jẹ̀ẹ́ láti pọ́n ọkàn rẹ̀ lójú.”
Àkànlò èdè yìí ni wọ́n fi ń sọ pé èèyàn kú.
Tàbí “gbógun ja.”
Tàbí “láti jẹ́ ọmọ ogun.”
Tàbí “àgọ́ olódi.”
Tàbí “ọkàn.”
Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.
Tàbí “ọkàn.”
Tàbí “ọkàn.”
Tàbí “ọkàn.”
Tàbí “ọkàn.”
Tàbí “ọkàn.”
Ṣékélì kan jẹ́ gíráàmù 11.4. Wo Àfikún B14.
Tàbí “ṣàtúnkọ́.”
Ó túmọ̀ sí “Abúlé Jáírì Tí Wọ́n Pàgọ́ Sí.”
Tàbí “ìlú tó yí i ká.”
Ní Héb., “ẹgbẹ́ ọmọ ogun kọ̀ọ̀kan.”
Ní Héb., “fi ọwọ́ tó ròkè.”
Tàbí “ère dídà.”
Ìyẹn, Òkun Òkú.
Ìyẹn, Òkun Ńlá, Òkun Mẹditaréníà.
Ìyẹn, Òkun Mẹditaréníà.
Tàbí “àbáwọlé Hámátì.”
Ìyẹn, adágún odò Jẹ́nẹ́sárẹ́tì tàbí Òkun Gálílì.
Ìgbọ̀nwọ́ kan jẹ́ sẹ̀ǹtímítà 44.5 (ínǹṣì 17.5). Wo Àfikún B14.
Tàbí “apààyàn.”
Tàbí “pa ọkàn.”
Tàbí “pa ọkàn.”
Ní Héb., “tó lúgọ dè é.”
Ní Héb., “láì lúgọ dè é.”
Tàbí “ọkàn.”
Ní Héb., “fi ẹnu sí i.”
Tàbí “ọkàn èyíkéyìí.”
Tàbí “ọkàn.”