ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • nwt Sáàmù 1:1-150:6
  • Sáàmù

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Sáàmù
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
Sáàmù

SÁÀMÙ

ÌWÉ KÌÍNÍ

(Sáàmù 1-41)

1 Aláyọ̀ ni ẹni tí kì í tẹ̀ lé ìmọ̀ràn àwọn èèyàn burúkú

Tí kì í dúró ní ọ̀nà àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀+

Tí kì í sì í jókòó lọ́dọ̀ àwọn ẹlẹ́gàn.+

 2 Ṣùgbọ́n òfin Jèhófà máa ń mú inú rẹ̀ dùn,+

Ó sì ń fi ohùn jẹ́ẹ́jẹ́ẹ́ ka* òfin Rẹ̀ tọ̀sántòru.+

 3 Ó máa dà bí igi tí a gbìn sétí odò,

Tó ń so èso ní àsìkò rẹ̀,

Tí ewé rẹ̀ kì í sì í rọ.

Gbogbo ohun tó bá ń ṣe yóò máa yọrí sí rere.+

 4 Àwọn èèyàn burúkú kò rí bẹ́ẹ̀;

Wọ́n dà bí ìyàngbò* tí afẹ́fẹ́ ń gbá lọ.

 5 Ìdí nìyẹn tí àwọn èèyàn burúkú kò fi ní lè dúró nígbà ìdájọ́;+

Tí àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ kò sì ní lè dúró ní àwùjọ àwọn olódodo.+

 6 Nítorí Jèhófà mọ ọ̀nà àwọn olódodo,+

Àmọ́ ọ̀nà àwọn èèyàn burúkú máa ṣègbé.+

2 Kí nìdí tí àwọn orílẹ̀-èdè fi ń ṣe awuyewuye

Tí àwọn èèyàn sì ń sọ ohun asán lẹ́nu wúyẹ́wúyẹ́?*+

 2 Àwọn ọba ayé dúró

Àwọn aláṣẹ sì kóra jọ*+

Láti dojú kọ Jèhófà àti ẹni àmì òróró* rẹ̀.+

 3 Wọ́n sọ pé: “Ẹ jẹ́ ká já ṣẹkẹ́ṣẹkẹ̀ wọn kúrò lára wa

Ká sì ju okùn wọn dà nù!”

 4 Ẹni tó wà lórí ìtẹ́ ní ọ̀run á rẹ́rìn-ín;

Jèhófà máa fi wọ́n ṣẹ̀sín.

 5 Ní àkókò yẹn, á sọ̀rọ̀ sí wọn nínú ìbínú rẹ̀

Á sì kó jìnnìjìnnì bá wọn nínú ìbínú rẹ̀ tó ń jó bí iná,

 6 Á sọ pé: “Èmi fúnra mi ti fi ọba mi jẹ+

Lórí Síónì,+ òkè mímọ́ mi.”

 7 Ẹ jẹ́ kí n kéde àṣẹ Jèhófà;

Ó sọ fún mi pé: “Ìwọ ni ọmọ mi;+

Òní ni mo di bàbá rẹ.+

 8 Béèrè lọ́wọ́ mi, màá fi àwọn orílẹ̀-èdè ṣe ogún fún ọ

Màá sì fi gbogbo ìkángun ayé ṣe ohun ìní fún ọ.+

 9 Wàá fi ọ̀pá àṣẹ onírin+ ṣẹ́ wọn,

Wàá sì fọ́ wọn túútúú bí ìkòkò amọ̀.”+

10 Nítorí náà, ẹ̀yin ọba, ẹ lo ìjìnlẹ̀ òye;

Ẹ gba ìtọ́sọ́nà,* ẹ̀yin onídàájọ́ ayé.

11 Ẹ fi ìbẹ̀rù sin Jèhófà,

Kí inú yín sì máa dùn nínú ìbẹ̀rù.

12 Ẹ bọlá fún ọmọ náà,*+ àìjẹ́ bẹ́ẹ̀ Ọlọ́run* máa bínú

Ẹ sì máa ṣègbé kúrò lójú ọ̀nà,+

Nítorí ìbínú Rẹ̀ tètè máa ń ru.

Aláyọ̀ ni gbogbo àwọn tó fi Í ṣe ibi ààbò.

Orin tí Dáfídì kọ nígbà tó ń sá lọ nítorí Ábúsálómù ọmọ rẹ̀.+

3 Jèhófà, kí nìdí tí àwọn ọ̀tá mi fi pọ̀ tó báyìí?+

Kí nìdí tí ọ̀pọ̀ èèyàn fi ń dìde sí mi?+

 2 Ọ̀pọ̀ ń sọ nípa mi* pé:

“Ọlọ́run ò ní gbà á sílẹ̀.”+ (Sélà)*

 3 Àmọ́, ìwọ Jèhófà ni apata tó yí mi ká,+

Ògo mi+ àti Ẹni tó ń gbé orí mi sókè.+

 4 Màá ké pe Jèhófà,

Yóò sì dá mi lóhùn láti òkè mímọ́ rẹ̀.+ (Sélà)

 5 Màá dùbúlẹ̀, màá sùn;

Màá sì jí ní àlàáfíà,

Nítorí Jèhófà ń tì mí lẹ́yìn.+

 6 Mi ò bẹ̀rù ẹgbẹẹgbẹ̀rún èèyàn

Tí wọ́n yí mi ká láti gbógun tì mí.+

 7 Dìde, Jèhófà! Gbà mí sílẹ̀,+ ìwọ Ọlọ́run mi!

Nítorí wàá gbá gbogbo àwọn ọ̀tá mi ní páárì ẹ̀rẹ̀kẹ́;

Wàá ká eyín àwọn ẹni burúkú.+

 8 Ti Jèhófà ni ìgbàlà.+

Ìbùkún rẹ wà lórí àwọn èèyàn rẹ. (Sélà)

Sí olùdarí; kí a kọ ọ́ pẹ̀lú àwọn ohun ìkọrin olókùn tín-ín-rín. Orin Dáfídì.

4 Nígbà tí mo bá pè, dá mi lóhùn, ìwọ Ọlọ́run mi olódodo.+

Ṣe ọ̀nà àbáyọ* fún mi nínú wàhálà mi.

Ṣe ojú rere sí mi, kí o sì gbọ́ àdúrà mi.

 2 Ẹ̀yin ọmọ èèyàn, ìgbà wo lẹ máa ṣíwọ́ sísọ iyì mi di àbùkù?

Ìgbà wo lẹ máa ṣíwọ́ nínífẹ̀ẹ́ ohun tí kò ní láárí, tí ẹ ó sì ṣíwọ́ wíwá ohun tí ó jẹ́ èké? (Sélà)

 3 Kí ẹ mọ̀ pé Jèhófà máa ṣìkẹ́ ẹni ìdúróṣinṣin rẹ̀ lọ́nà àrà ọ̀tọ̀;*

Jèhófà máa gbọ́ nígbà tí mo bá ké pè é.

 4 Tí inú bá bí yín, ẹ má ṣẹ̀.+

Ẹ sọ ohun tí ẹ ní í sọ nínú ọkàn yín, lórí ibùsùn yín, kí ẹ sì dákẹ́ jẹ́ẹ́. (Sélà)

 5 Ẹ rú ẹbọ òdodo,

Kí ẹ sì gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà.+

 6 Ọ̀pọ̀ ló ń sọ pé: “Ta ló máa jẹ́ ká rí ohun rere?”

Jèhófà, jẹ́ kí ìmọ́lẹ̀ ojú rẹ tàn sí wa lára.+

 7 O ti fi ayọ̀ púpọ̀ kún ọkàn mi

Ju ti àwọn tó ní ọ̀pọ̀ ọkà àti wáìnì tuntun nígbà ìkórè.

 8 Màá dùbúlẹ̀, màá sì sùn ní àlàáfíà,+

Nítorí ìwọ nìkan, Jèhófà, ló ń mú kí n máa gbé láìséwu.+

Sí olùdarí fún Néhílótì.* Orin Dáfídì.

5 Fetí sí ọ̀rọ̀ mi, Jèhófà;+

Fiyè sí ẹ̀dùn ọkàn mi.

 2 Fetí sí igbe ìrànlọ́wọ́ mi,

Ìwọ Ọba mi àti Ọlọ́run mi, torí pé ìwọ ni mò ń gbàdúrà sí.

 3 Ní òwúrọ̀, Jèhófà, wàá gbọ́ ohùn mi;+

Ní òwúrọ̀, màá sọ ohun tó ń jẹ mí lọ́kàn fún ọ,+ màá sì dúró dè ọ́.

 4 Nítorí ìwọ kì í ṣe Ọlọ́run tó fẹ́ràn ìwà burúkú;+

Kò sí ẹni burúkú tó lè dúró lọ́dọ̀ rẹ.+

 5 Kò sí agbéraga tó lè dúró níwájú rẹ.

O kórìíra gbogbo àwọn tó ń hùwà ibi;+

 6 Wàá pa àwọn tó ń parọ́ run.+

Jèhófà kórìíra àwọn tó ń hu ìwà ipá àti ìwà ẹ̀tàn.*+

 7 Àmọ́ màá wá sínú ilé rẹ+ nítorí ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ tó lágbára;+

Màá forí balẹ̀ ní ìdojúkọ tẹ́ńpìlì mímọ́* rẹ nínú ẹ̀rù tí mo ní fún ọ.+

 8 Jèhófà, ṣamọ̀nà mi nínú òdodo rẹ nítorí àwọn ọ̀tá mi;

Mú kí ọ̀nà rẹ là fún mi.+

 9 Nítorí kò sí èyí tó ṣeé gbára lé nínú ọ̀rọ̀ wọn;

Èrò ibi ló kún inú wọn;

Sàréè tó ṣí sílẹ̀ ni ọ̀fun wọn;

Wọ́n ń fi ẹnu wọn pọ́nni.*+

10 Àmọ́ Ọlọ́run á dá wọn lẹ́bi;

Èrò ibi wọn á mú kí wọ́n ṣubú.+

Kí a lé wọn dà nù torí ẹ̀ṣẹ̀ wọn tó pọ̀ gan-an,

Nítorí wọ́n ti ṣọ̀tẹ̀ sí ọ.

11 Àmọ́ gbogbo àwọn tó fi ọ́ ṣe ibi ààbò á máa yọ̀;+

Ìgbà gbogbo ni wọ́n á máa kígbe ayọ̀.

Wàá dáàbò bo ọ̀nà àbáwọlé wọn,

Àwọn tó nífẹ̀ẹ́ orúkọ rẹ yóò sì máa yọ̀ nínú rẹ.

12 Jèhófà, wàá bù kún ẹni tó bá jẹ́ olódodo;

Wàá fi ojú rere dáàbò bò wọ́n bí apata ńlá.+

Sí olùdarí; kí a kọ ọ́ pẹ̀lú àwọn ohun ìkọrin olókùn tín-ín-rín tí a yí sí Ṣẹ́mínítì.* Orin Dáfídì.

6 Jèhófà, má ṣe bá mi wí nínú ìbínú rẹ,

Má sì tọ́ mi sọ́nà nínú ìrunú rẹ.+

 2 Ṣojú rere sí mi,* Jèhófà, nítorí ó ti ń rẹ̀ mí.

Wò mí sàn, Jèhófà,+ nítorí àwọn egungun mi ń gbọ̀n.

 3 Bẹ́ẹ̀ ni, ìdààmú ti bá mi* gidigidi,+

Torí náà, mò ń bi ọ́, Jèhófà, ìgbà wo ló máa dópin?+

 4 Pa dà, Jèhófà, kí o sì gbà mí* sílẹ̀;+

Gbà mí là nítorí ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀.+

 5 Nítorí òkú kò lè sọ nípa* rẹ;

Àbí, ta ló lè yìn ọ́ nínú Isà Òkú?*+

 6 Àárẹ̀ ti mú mi nítorí ẹ̀dùn ọkàn mi;+

Láti òru mọ́jú ni omijé mi ń rin ibùsùn mi gbingbin;*

Ẹkún mi ti fi omi kún àga tìmùtìmù mi.+

 7 Ìbànújẹ́ ti sọ ojú mi di bàìbàì;+

Ojú mi ti ṣú* nítorí gbogbo àwọn tó ń halẹ̀ mọ́ mi.

 8 Ẹ kúrò lọ́dọ̀ mi, gbogbo ẹ̀yin tó ń hùwà burúkú,

Nítorí pé Jèhófà yóò gbọ́ igbe ẹkún mi.+

 9 Jèhófà yóò gbọ́ ẹ̀bẹ̀ mi fún ojú rere;+

Jèhófà yóò dáhùn àdúrà mi.

10 Ojú á ti gbogbo àwọn ọ̀tá mi, ìdààmú á sì bá wọn;

Ìtìjú òjijì á mú wọn sá pa dà.+

Orin arò* Dáfídì tí ó kọ sí Jèhófà nítorí àwọn ọ̀rọ̀ Kúṣì ọmọ Bẹ́ńjámínì.

7 Jèhófà Ọlọ́run mi, ìwọ ni mo fi ṣe ibi ààbò mi.+

Gbà mí lọ́wọ́ gbogbo àwọn tó ń ṣe inúnibíni sí mi, kí o sì dá mi nídè.+

 2 Àìjẹ́ bẹ́ẹ̀, wọ́n á fà mí* ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ bíi kìnnìún,+

Wọ́n á gbé mi lọ láìsí ẹni tó máa gbà mí sílẹ̀.

 3 Jèhófà Ọlọ́run mi, tí mo bá jẹ̀bi nínú ọ̀ràn yìí,

Tí mo bá ṣe àìtọ́,

 4 Tí mo bá ṣe àìdáa sí ẹni tó ṣe rere sí mi,+

Tàbí kẹ̀, tí mo bá kó ẹrù ọ̀tá mi lọ láìnídìí,*

 5 Kí ọ̀tá máa lépa mi, kó sì bá mi;*

Kó tẹ ẹ̀mí mi mọ́lẹ̀

Kó sì mú kí ògo mi pa rẹ́ mọ́ ilẹ̀. (Sélà)

 6 Dìde nínú ìbínú rẹ, Jèhófà;

Gbéra láti kojú àwọn ọ̀tá mi nínú ìbínú wọn;+

Jí nítorí mi, kí o sì mú kí wọ́n ṣe ìdájọ́ òdodo.+

 7 Kí àwọn orílẹ̀-èdè yí ọ ká;

Kí o sì gbéjà kò wọ́n látòkè.

 8 Jèhófà yóò ṣe ìdájọ́ àwọn èèyàn.+

Ṣe ìdájọ́ mi, Jèhófà, gẹ́gẹ́ bí òdodo mi

Àti gẹ́gẹ́ bí ìwà títọ́ mi.+

 9 Jọ̀wọ́, fòpin sí ìwà ibi àwọn ẹni burúkú.

Àmọ́, fìdí olódodo múlẹ̀,+

Nítorí pé Ọlọ́run olódodo ni ọ́,+ tó ń ṣàyẹ̀wò ọkàn+ àti inú lọ́hùn-ún.*+

10 Ọlọ́run ni apata mi,+ Olùgbàlà àwọn tí ọkàn wọn dúró ṣinṣin.+

11 Ọlọ́run jẹ́ Onídàájọ́ òdodo,+

Ọlọ́run sì ń kéde ìdájọ́ rẹ̀* lójoojúmọ́.

12 Bí ẹnikẹ́ni kò bá ronú pìwà dà,+ Á pọ́n idà rẹ̀;+

Á tẹ ọrun rẹ̀, á sì mú kó wà ní sẹpẹ́.+

13 Ó ń ṣètò àwọn ohun ìjà rẹ̀ tó ń ṣekú pani sílẹ̀;

Ó ń mú kí àwọn ọfà rẹ̀ tó ń jó fòfò wà ní sẹpẹ́.+

14 Wo ẹni tó lóyún ìwà ìkà;

Ọmọ* ìjàngbọ̀n wà nínú rẹ̀, ó sì bí èké.+

15 Ó ti wa kòtò, ó sì gbẹ́ ẹ jìn,

Àmọ́ ó já sínú ihò tí òun fúnra rẹ̀ gbẹ́.+

16 Wàhálà tó dá sílẹ̀ á pa dà sí orí òun fúnra rẹ̀;+

Ìwà ipá rẹ̀ á sì já lé àtàrí rẹ̀.

17 Màá yin Jèhófà nítorí òdodo rẹ̀,+

Màá sì fi orin yin* orúkọ Jèhófà+ Ẹni Gíga Jù Lọ.+

Sí olùdarí; lórí Gítítì.* Orin Dáfídì.

8 Jèhófà Olúwa wa, orúkọ rẹ mà níyì ní gbogbo ayé o;

O ti gbé ògo rẹ ga, kódà ó ga ju ọ̀run lọ!*+

 2 O fìdí agbára rẹ múlẹ̀ láti ẹnu àwọn ọmọdé àti àwọn ọmọ jòjòló+

Nítorí àwọn elénìní rẹ,

Kí o lè pa ọ̀tá àti olùgbẹ̀san lẹ́nu mọ́.

 3 Nígbà tí mo rí ọ̀run rẹ, àwọn iṣẹ́ ìka rẹ,

Òṣùpá àti àwọn ìràwọ̀ tí o ti ṣètò sílẹ̀,+

 4 Kí ni ẹni kíkú jẹ́ tí o fi ń fi í sọ́kàn

Àti ọmọ aráyé tí o fi ń tọ́jú rẹ̀?+

 5 O mú kó rẹlẹ̀ díẹ̀ ju àwọn ẹni bí Ọlọ́run,*

O sì fi ògo àti ọlá ńlá dé e ládé.

 6 O fún un ní àṣẹ lórí àwọn iṣẹ́ ọwọ́ rẹ;+

O ti fi ohun gbogbo sábẹ́ ẹsẹ̀ rẹ̀:

 7 Gbogbo àwọn agbo ẹran àti màlúù,

Àti àwọn ẹran inú igbó,*+

 8 Àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run àti ẹja inú òkun,

Ohunkóhun tó ń gba inú òkun kọjá.

 9 Jèhófà Olúwa wa, orúkọ rẹ mà níyì ní gbogbo ayé o!

Sí olùdarí; lórí Muti-lábénì.* Orin Dáfídì.

א [Áléfì]

9 Jèhófà, màá fi gbogbo ọkàn mi yìn ọ́;

Màá sọ nípa gbogbo iṣẹ́ àgbàyanu rẹ.+

 2 Ṣe ni inú mi á máa dùn, tí màá sì máa yọ̀ nínú rẹ;

Màá fi orin yin* orúkọ rẹ, ìwọ Ẹni Gíga Jù Lọ.+

ב [Bétì]

 3 Nígbà tí àwọn ọ̀tá mi bá sá pa dà,+

Wọ́n á ṣubú, wọ́n á sì ṣègbé kúrò níwájú rẹ.

 4 Nítorí pé o gbèjà mi lórí ẹ̀tọ́ mi;

O jókòó sórí ìtẹ́ rẹ, o sì ń fi òdodo ṣe ìdájọ́.+

ג [Gímélì]

5 O ti bá àwọn orílẹ̀-èdè wí,+ o sì ti pa àwọn ẹni burúkú run,

O ti nu orúkọ wọn kúrò títí láé àti láéláé.

6 Ọ̀tá ti pa run títí láé;

O ti fa àwọn ìlú wọn tu,

Wọn yóò sì di ẹni ìgbàgbé.+

ה [Híì]

7 Àmọ́ Jèhófà wà lórí ìtẹ́ títí láé;+

Ó ti fìdí ìtẹ́ rẹ̀ múlẹ̀ gbọn-in láti máa ṣe ìdájọ́ òdodo.+

8 Yóò fi òdodo ṣe ìdájọ́ ilẹ̀ ayé tí à ń gbé;*+

Yóò dá ẹjọ́ òdodo fún àwọn orílẹ̀-èdè.+

ו [Wọ́ọ̀]

 9 Jèhófà yóò di ibi ààbò* fún àwọn tí à ń ni lára,+

Ibi ààbò ní àkókò wàhálà.+

10 Àwọn tó mọ orúkọ rẹ yóò gbẹ́kẹ̀ lé ọ;+

Jèhófà, ìwọ kì yóò pa àwọn tó ń wá ọ tì láé.+

ז [Sáyìn]

11 Ẹ kọ orin ìyìn sí Jèhófà, ẹni tó ń gbé ní Síónì;

Ẹ jẹ́ kí àwọn èèyàn mọ àwọn ohun tí ó ṣe.+

12 Nítorí Ẹni tó ń gbẹ̀san ẹ̀jẹ̀ wọn ń rántí wọn;+

Kò ní gbàgbé igbe àwọn tí ìyà ń jẹ.+

ח [Hétì]

13 Ṣojú rere sí mi, Jèhófà; wo ìyà tí àwọn tó kórìíra mi fi ń jẹ mí,

Ìwọ tó gbé mi dìde láti àwọn ẹnubodè ikú,+

14 Kí n lè máa kéde àwọn iṣẹ́ rẹ tí ó yẹ fún ìyìn ní àwọn ẹnubodè ọmọbìnrin Síónì,+

Kí àwọn iṣẹ́ ìgbàlà rẹ sì lè máa mú inú mi dùn.+

ט [Tétì]

15 Àwọn orílẹ̀-èdè ti rì sínú kòtò tí wọ́n gbẹ́;

Ẹsẹ̀ wọn ti kó sínú àwọ̀n tí àwọn fúnra wọn dẹ pa mọ́.+

16 Àwọn ìdájọ́ tí Jèhófà ń mú ṣẹ ń jẹ́ kí a mọ̀ ọ́n.+

Iṣẹ́ ọwọ́ ẹni burúkú ti dẹkùn mú òun fúnra rẹ̀.+

Hígáíónì.* (Sélà)

י [Yódì]

17 Àwọn èèyàn burúkú á sá pa dà, wọ́n á sì forí lé Isà Òkú,*

Gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè tó gbàgbé Ọlọ́run.

18 Àmọ́, a kò ní gbàgbé àwọn aláìní títí lọ;+

Bẹ́ẹ̀ ni ìrètí àwọn oníwà pẹ̀lẹ́ kò ní já sí asán láé.+

כ [Káfì]

19 Dìde, Jèhófà! Má ṣe jẹ́ kí ẹni kíkú borí.

Jẹ́ kí àwọn orílẹ̀-èdè gba ìdájọ́ níwájú rẹ.+

 20 Dẹ́rù bà wọ́n, Jèhófà,+

Jẹ́ kí àwọn orílẹ̀-èdè mọ̀ pé ẹni kíkú lásán ni wọ́n. (Sélà)

ל [Lámédì]

10 Jèhófà, kí nìdí tí o fi dúró lókèèrè?

Kí nìdí tí o fi fara pa mọ́ ní àkókò wàhálà?+

 2 Ẹni burúkú ń fi ìgbéraga lépa ẹni tí kò ní olùrànlọ́wọ́,+

Àmọ́ èrò ibi tó gbà máa yí dà lé e lórí.+

 3 Ẹni burúkú ń fọ́nnu nítorí ìfẹ́ ọkàn ara rẹ̀,+

Ó sì ń súre fún àwọn olójúkòkòrò;*

נ [Núnì]

Kì í bọ̀wọ̀ fún Jèhófà.

 4 Ìgbéraga kì í jẹ́ kí ẹni burúkú ṣe ìwádìí kankan;

Gbogbo èrò rẹ̀ ni pé: “Kò sí Ọlọ́run.”+

 5 Àwọn ọ̀nà rẹ̀ ń yọrí sí rere,+

Àmọ́ àwọn ìdájọ́ rẹ ga kọjá òye rẹ̀;+

Ó ń fi gbogbo àwọn ọ̀tá rẹ̀ ṣẹ̀sín.*

 6 Ó ń sọ lọ́kàn rẹ̀ pé: “Mìmì kan ò ní mì mí;*

Láti ìran dé ìran

Mi ò ní rí àjálù láé.”+

פ [Péè]

 7 Ègún, irọ́ àti ìhàlẹ̀ kún ẹnu rẹ̀;+

Ìjàngbọ̀n àti jàǹbá wà lábẹ́ ahọ́n rẹ̀.+

 8 Ó ń lúgọ lẹ́gbẹ̀ẹ́ àwọn ibùdó;

Ó ń pa àwọn aláìṣẹ̀ láti ibi tó fara pa mọ́ sí.+

ע [Áyìn]

Ojú rẹ̀ ń wá àwọn tó rin àrìnfẹsẹ̀sí.+

 9 Ó ń dúró níbi tó fara pa mọ́ sí bíi kìnnìún nínú ihò rẹ̀.*+

Ó ń dúró láti mú ẹni tí kò ní olùrànlọ́wọ́.

Ó ń mú ẹni tí kò ní olùrànlọ́wọ́ nígbà tó bá pa àwọ̀n rẹ̀ dé.+

10 Ẹni tó bá kó sí i lọ́wọ́ yóò di àtẹ̀rẹ́, yóò sì ṣubú lulẹ̀;

Àwọn tó rin àrìnfẹsẹ̀sí yóò kó sínú akóló rẹ̀.*

11 Ó sọ lọ́kàn rẹ̀ pé: “Ọlọ́run ti gbàgbé.+

Ó ti gbé ojú rẹ̀ kúrò.

Kò sì ní fiyè sí i láé.”+

ק [Kófì]

12 Jèhófà dìde.+ Ọlọ́run, gbé ọwọ́ rẹ sókè.+

Má gbàgbé àwọn tí kò ní olùrànlọ́wọ́.+

13 Kí nìdí tí ẹni burúkú kò fi bọ̀wọ̀ fún Ọlọ́run?

Ó sọ lọ́kàn rẹ̀ pé: “O ò ní pè mí wá jíhìn.”

ר [Réṣì]

14 Àmọ́, o rí ìjàngbọ̀n àti ìdààmú.

Ò ń wò ó, o sì gbé ìgbésẹ̀.+

Ọ̀dọ̀ rẹ ni àwọn tó rin àrìnfẹsẹ̀sí yíjú sí;+

Ìwọ ni olùrànlọ́wọ́ ọmọ aláìníbaba.*+

ש [Ṣínì]

15 Ṣẹ́ apá ẹni burúkú àti ẹni ibi,+

Kó lè jẹ́ pé nígbà tí o bá wá ìwà burúkú rẹ̀,

O ò ní rí i mọ́.

16 Jèhófà ni Ọba títí láé àti láéláé.+

Àwọn orílẹ̀-èdè ti ṣègbé kúrò láyé.+

ת [Tọ́ọ̀]

17 Àmọ́ Jèhófà, wàá gbọ́ ẹ̀bẹ̀ àwọn oníwà pẹ̀lẹ́.+

Wàá mú ọkàn wọn dúró ṣinṣin,+ wàá sì fiyè sí wọn.+

18 Wàá dá ẹjọ́ òdodo fún ọmọ aláìníbaba àti ẹni tí a ni lára,+

Kí ẹni kíkú lásánlàsàn* má bàa dẹ́rù bà wọ́n mọ́.+

Sí olùdarí. Ti Dáfídì.

11 Jèhófà ni mo fi ṣe ibi ààbò mi.+

Torí náà, ẹ ṣe lè sọ fún mi* pé:

“Fò lọ sórí òkè bí ẹyẹ!

 2 Wo bí àwọn ẹni burúkú ṣe tẹ ọrun;

Wọ́n fi ọfà wọn sára okùn ọrun,*

Kí wọ́n lè ta á látinú òkùnkùn lu àwọn tí ọkàn wọn dúró ṣinṣin.

 3 Nígbà tí ìpìlẹ̀* bá bà jẹ́,

Kí ni olódodo lè ṣe?”

 4 Jèhófà wà nínú tẹ́ńpìlì mímọ́ rẹ̀.+

Ìtẹ́ Jèhófà wà ní ọ̀run.+

Ojú rẹ̀ ń wò, ojú rẹ̀ tó rí ohun gbogbo* ń ṣàyẹ̀wò àwọn ọmọ èèyàn.+

 5 Jèhófà ń ṣàyẹ̀wò olódodo àti ẹni burúkú;+

Ó* kórìíra ẹni tó bá nífẹ̀ẹ́ ìwà ipá.+

 6 Yóò dẹ ọ̀pọ̀ pańpẹ́ fún* àwọn ẹni burúkú;

Iná, imí ọjọ́+ àti ẹ̀fúùfù gbígbóná ni yóò wà nínú ife wọn.

 7 Nítorí olódodo ni Jèhófà;+ ó nífẹ̀ẹ́ àwọn iṣẹ́ òdodo.+

Àwọn adúróṣinṣin yóò rí ojú* rẹ̀.+

Sí olùdarí; kí a yí i sí Ṣẹ́mínítì.* Orin Dáfídì.

12 Gbà mí Jèhófà, nítorí kò sí ẹni ìdúróṣinṣin mọ́;

Àwọn olóòótọ́ ti pòórá láàárín àwọn èèyàn.

 2 Irọ́ ni wọ́n ń pa fún ara wọn;

Wọ́n ń fi ètè wọn pọ́nni,* wọ́n sì ń fi ọkàn ẹ̀tàn* sọ̀rọ̀.+

 3 Jèhófà máa gé gbogbo ètè tó ń pọ́nni kúrò

Àti ahọ́n tó ń sọ̀rọ̀ ìgbéraga,+

 4 Àwọn tó ń sọ pé: “Ahọ́n wa la máa fi ṣàṣeyọrí.

Bó ṣe wù wá ni à ń lo ètè wa;

Ta ló máa jẹ ọ̀gá lé wa lórí?”+

 5 “Nítorí ìnira àwọn tí ìyà ń jẹ,

Nítorí ìkérora àwọn aláìní,+

Màá dìde láti gbé ìgbésẹ̀,” ni Jèhófà wí.

“Màá gbà wọ́n lọ́wọ́ àwọn tó kórìíra wọn.”*

 6 Àwọn ọ̀rọ̀ Jèhófà mọ́;+

Wọ́n dà bíi fàdákà tí a yọ́ mọ́ nínú iná ìléru tí wọ́n fi amọ̀ ṣe,* èyí tí a yọ́ mọ́ ní ìgbà méje.

 7 Jèhófà, wàá máa ṣọ́ wọn;+

Wàá dáàbò bo kálukú wọn lọ́wọ́ ìran yìí títí láé.

 8 Àwọn ẹni burúkú ń rìn káàkiri fàlàlà

Nítorí pé àwọn ọmọ èèyàn ń gbé ìwà ìbàjẹ́ lárugẹ.+

Sí olùdarí. Orin Dáfídì.

13 Jèhófà, ìgbà wo lo máa gbàgbé mi dà? Ṣé títí láé ni?

Ìgbà wo lo máa gbé ojú rẹ pa mọ́ fún mi dà?+

 2 Ìgbà wo ni mi* ò ní dààmú mọ́,

Tí ẹ̀dùn ọkàn mi ojoojúmọ́ á sì dópin?

Ìgbà wo ni ọ̀tá mi ò ní jẹ gàba lé mi lórí mọ́?+

 3 Bojú wò mí, kí o sì dá mi lóhùn, Jèhófà Ọlọ́run mi.

Tan ìmọ́lẹ̀ sí ojú mi, kí n má bàa sun oorun ikú,

 4 Kí ọ̀tá mi má bàa sọ pé: “Mo ti ṣẹ́gun rẹ̀!”

Má ṣe jẹ́ kí àwọn tó ń ta kò mí yọ̀ lórí ìṣubú mi.+

 5 Ní tèmi, ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ ni mo gbẹ́kẹ̀ lé;+

Àwọn iṣẹ́ ìgbàlà rẹ yóò máa mú ọkàn mi yọ̀.+

 6 Ṣe ni èmi yóò máa kọrin sí Jèhófà, nítorí ó ti san èrè fún mi lọ́pọ̀lọpọ̀.*+

Sí olùdarí. Ti Dáfídì.

14 Òmùgọ̀* sọ lọ́kàn rẹ̀ pé:

“Kò sí Jèhófà.”+

Ìwà ìbàjẹ́ ni wọ́n ń hù, ìṣesí wọn sì jẹ́ ohun ìríra;

Kò sí ẹni tó ń ṣe rere.+

 2 Àmọ́ Jèhófà ń bojú wo àwọn ọmọ èèyàn láti ọ̀run

Láti rí i bóyá ẹnì kan wà tó ní ìjìnlẹ̀ òye, bóyá ẹnì kan wà tó ń wá Jèhófà.+

 3 Gbogbo wọn ti kúrò lójú ọ̀nà;+

Gbogbo wọn jẹ́ oníwà ìbàjẹ́.

Kò sí ẹni tó ń ṣe rere,

Kò tiẹ̀ sí ẹyọ kan.

 4 Ṣé kò yé ìkankan lára àwọn oníwà burúkú ni?

Wọ́n ń ya àwọn èèyàn mi jẹ bí ẹni ń jẹ búrẹ́dì.

Wọn ò ké pe Jèhófà.

 5 Àmọ́, jìnnìjìnnì á bò wọ́n,+

Nítorí Jèhófà wà pẹ̀lú ìran àwọn olódodo.

 6 Ẹ̀yin oníwà burúkú fẹ́ da èrò aláìní rú,

Àmọ́ Jèhófà ni ibi ààbò rẹ̀.+

 7 Ká ní ìgbàlà Ísírẹ́lì lè wá láti Síónì+ ni!

Nígbà tí Jèhófà bá kó àwọn èèyàn rẹ̀ tó wà lóko ẹrú pa dà,

Kí inú Jékọ́bù dùn, kí Ísírẹ́lì sì yọ̀.

Orin Dáfídì.

15 Jèhófà, ta ló lè jẹ́ àlejò nínú àgọ́ rẹ?

Ta ló lè máa gbé ní òkè mímọ́ rẹ?+

 2 Ẹni tó ń rìn láìlẹ́bi,*+

Tó ń ṣe ohun tí ó tọ́+

Tó sì ń sọ òtítọ́ nínú ọkàn rẹ̀.+

 3 Kò fi ahọ́n rẹ̀ bani jẹ́,+

Kò ṣe ohun búburú kankan sí ọmọnìkejì rẹ̀,+

Kò sì ba àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ lórúkọ jẹ́.*+

 4 Kì í bá ẹnikẹ́ni tó jẹ́ oníwàkiwà kẹ́gbẹ́,+

Àmọ́ ó máa ń bọlá fún àwọn tó bẹ̀rù Jèhófà.

Kì í yẹ àdéhùn,* kódà tó bá máa pa á lára.+

 5 Kì í yáni lówó èlé,+

Kì í gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀ láti gbógun ti aláìṣẹ̀.+

Ẹni tó bá ń ṣe àwọn nǹkan yìí, mìmì kan ò ní mì í láé.*+

Míkítámù* ti Dáfídì.

16 Dáàbò bò mí, Ọlọ́run, nítorí ìwọ ni mo fi ṣe ibi ààbò.+

 2 Mo ti sọ fún Jèhófà pé: “Ìwọ ni Jèhófà, Orísun oore mi.

 3 Àwọn ẹni mímọ́ tó wà láyé

Àti àwọn ọlọ́lá, ń mú inú mi dùn jọjọ.”+

 4 Àwọn tó ń tẹ̀ lé ọlọ́run mìíràn ń sọ ìbànújẹ́ wọn di púpọ̀.+

Mi ò ní bá wọn da ọrẹ ohun mímu ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀,

Bẹ́ẹ̀ ni ètè mi ò ní dárúkọ wọn.*+

 5 Jèhófà ni ìpín mi, apá tí ó kàn mí+ àti ife mi.+

O dáàbò bo ogún mi.

 6 A ti díwọ̀n àwọn ibi tó dáa jáde fún mi.

Bẹ́ẹ̀ ni, ogún mi tẹ́ mi lọ́rùn.+

 7 Màá yin Jèhófà, ẹni tó fún mi ní ìmọ̀ràn.+

Kódà láàárín òru, èrò inú mi* ń tọ́ mi sọ́nà.+

 8 Mo gbé Jèhófà síwájú mi nígbà gbogbo.+

Torí pé ó wà ní ọwọ́ ọ̀tún mi, mìmì kan ò ní mì mí.*+

 9 Nítorí náà, ọkàn mi ń yọ̀, gbogbo ara* mi ń dunnú.

Mo* sì ń gbé lábẹ́ ààbò.

10 Torí o ò ní fi mí sílẹ̀* nínú Isà Òkú.*+

O ò ní jẹ́ kí ẹni ìdúróṣinṣin rẹ rí kòtò.*+

11 O jẹ́ kí n mọ ọ̀nà ìyè.+

Ayọ̀ púpọ̀+ wà ní iwájú* rẹ,

Ìdùnnú* sì wà ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ títí láé.

Àdúrà Dáfídì.

17 Jèhófà, gbọ́ ẹ̀bẹ̀ mi fún ìdájọ́ òdodo;

Fiyè sí igbe mi fún ìrànlọ́wọ́;

Fetí sí àdúrà tí mo gbà láìṣẹ̀tàn.+

 2 Kí o ṣe ìpinnu tí ó tọ́ nítorí mi;+

Kí ojú rẹ rí ohun tí ó tọ́.

 3 O ti ṣàyẹ̀wò ọkàn mi, o ti bẹ̀ mí wò ní òru;+

O ti yọ́ mi mọ́;+

Wàá rí i pé mi ò ní èrò ibi kankan lọ́kàn,

Ẹnu mi kò sì dẹ́ṣẹ̀.

 4 Ohunkóhun tí àwọn èèyàn ì báà máa ṣe,

Nítorí ọ̀rọ̀ rẹ, mo yẹra fún ọ̀nà àwọn ọlọ́ṣà.+

 5 Má ṣe jẹ́ kí ìṣísẹ̀ mi kúrò ní ọ̀nà rẹ

Kí n má bàa kọsẹ̀.+

 6 Ọlọ́run, mò ń ké pè ọ́, torí mo mọ̀ pé wàá dá mi lóhùn.+

Tẹ́tí sí mi.* Gbọ́ ọ̀rọ̀ mi.+

 7 Fi ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ hàn lọ́nà àgbàyanu,+

Ìwọ Olùgbàlà àwọn tó ń wá ààbò ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ

Kí ọwọ́ àwọn tó ń ṣọ̀tẹ̀ sí ọ má bàa tẹ̀ wọ́n.

 8 Dáàbò bò mí bí ọmọlójú rẹ;+

Fi mí pa mọ́ sábẹ́ òjìji ìyẹ́ apá rẹ.+

 9 Dáàbò bò mí lọ́wọ́ àwọn ẹni burúkú tó ń gbéjà kò mí.

Lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá alénimádẹ̀yìn* tí wọ́n yí mi ká.+

10 Wọ́n ti yigbì;*

Wọ́n ń fi ẹnu wọn sọ̀rọ̀ ìgbéraga;

11 Ní báyìí, wọ́n ti ká wa mọ́;+

Wọ́n ń wá ọ̀nà tí wọ́n á fi gbé wa ṣubú.*

12 Ó dà bíi kìnnìún tó fẹ́ fa ẹran ya,

Bí ọmọ kìnnìún tó lúgọ síbi ìkọ̀kọ̀.

13 Dìde Jèhófà, kí o kò ó lójú+ kí o sì mú un balẹ̀;

Fi idà rẹ gbà mí* lọ́wọ́ ẹni burúkú;

14 Jèhófà, fi ọwọ́ rẹ gbà mí sílẹ̀,

Lọ́wọ́ àwọn èèyàn ayé* yìí, àwọn tí ìpín wọn jẹ́ ti ayé yìí,+

Àwọn tí o fún ní àwọn ohun rere tí o ti pèsè,+

Àwọn tí wọ́n fi ogún sílẹ̀ fún ọmọ púpọ̀.

15 Àmọ́ ní tèmi, màá rí ojú rẹ nínú òdodo;

Ó tẹ́ mi lọ́rùn láti máa jí rí ọ.*+

Sí olùdarí. Látọ̀dọ̀ Dáfídì ìránṣẹ́ Jèhófà, tí ó kọ ọ̀rọ̀ yìí lórin sí Jèhófà ní ọjọ́ tí Jèhófà gbà á lọ́wọ́ gbogbo àwọn ọ̀tá rẹ̀ àti lọ́wọ́ Sọ́ọ̀lù. Ó sọ pé:+

18 Jèhófà, mo nífẹ̀ẹ́ rẹ, ìwọ ni okun mi.+

 2 Jèhófà ni àpáta gàǹgà mi àti odi ààbò mi àti Ẹni tó ń gbà mí sílẹ̀.+

Ọlọ́run mi ni àpáta mi,+ ẹni tí mo fi ṣe ibi ààbò,

Apata mi àti ìwo* ìgbàlà mi,* ibi ààbò mi.*+

 3 Mo ké pe Jèhófà, ẹni tí ìyìn yẹ,

Yóò sì gbà mí lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá mi.+

 4 Àwọn okùn ikú yí mi ká;+

Àwọn ọkùnrin tí kò ní láárí ya lù mí bí omi.+

 5 Àwọn okùn Isà Òkú* yí mi ká;

Ikú dẹ pańpẹ́ síwájú mi.+

 6 Mo ké pe Jèhófà nínú wàhálà mi,

Mo sì ń kígbe sí Ọlọ́run mi fún ìrànlọ́wọ́.

Ó gbọ́ ohùn mi láti tẹ́ńpìlì rẹ̀,+

Igbe tí mo ké sọ́dọ̀ rẹ̀ fún ìrànlọ́wọ́ sì dé etí rẹ̀.+

 7 Nígbà náà, ayé bẹ̀rẹ̀ sí í mì, ó sì ń mì jìgìjìgì;+

Ìpìlẹ̀ àwọn òkè mì,

Wọ́n sì ń mì síwá-sẹ́yìn nítorí a ti mú un bínú.+

 8 Èéfín jáde láti ihò imú rẹ̀,

Iná tó ń jóni run jáde láti ẹnu rẹ̀,+

Ẹyin iná sì ń jó láti ọ̀dọ̀ rẹ̀.

 9 Ó tẹ ọ̀run wálẹ̀ bí ó ṣe ń sọ̀ kalẹ̀.+

Ìṣúdùdù tó kàmàmà sì wà lábẹ́ ẹsẹ̀ rẹ̀.+

10 Ó gun kérúbù, ó sì ń fò bọ̀.+

Ó ń bọ̀ ṣòòrò wálẹ̀ lórí ìyẹ́ apá áńgẹ́lì kan.*+

11 Ó wá fi òkùnkùn bo ara rẹ̀,+

Ó bò ó yí ká bí àgọ́,

Nínú ojú ọ̀run tó ṣú dẹ̀dẹ̀.+

12 Láti inú ìmọ́lẹ̀ tó wà níwájú rẹ̀,

Yìnyín àti ẹyin iná gba inú àwọsánmà jáde.

13 Nígbà náà, Jèhófà bẹ̀rẹ̀ sí í sán ààrá ní ọ̀run;+

Ẹni Gíga Jù Lọ mú kí a gbọ́ ohùn rẹ̀+

Pẹ̀lú yìnyín àti ẹyin iná.

14 Ó ta àwọn ọfà rẹ̀, ó sì tú wọn ká;+

Ó ju mànàmáná rẹ̀, ó sì kó wọn sínú ìdàrúdàpọ̀.+

15 Ìsàlẹ̀ odò* hàn síta;+

Àwọn ìpìlẹ̀ ayé hàn síta nítorí ìbáwí rẹ, Jèhófà,

Nípa èémí tó tú jáde ní ihò imú rẹ.+

16 Ó na ọwọ́ rẹ̀ láti òkè;

Ó mú mi, ó sì fà mí jáde látinú omi jíjìn.+

17 Ó gbà mí lọ́wọ́ ọ̀tá mi alágbára,+

Lọ́wọ́ àwọn tó kórìíra mi, tí wọ́n sì lágbára jù mí lọ.+

18 Wọ́n kò mí lójú ní ọjọ́ àjálù mi,+

Ṣùgbọ́n Jèhófà ni alátìlẹyìn mi.

19 Ó mú mi jáde wá sí ibi ààbò;*

Ó gbà mí sílẹ̀ nítorí pé inú rẹ̀ dùn sí mi.+

20 Jèhófà san èrè fún mi nítorí òdodo mi;+

Ó san èrè fún mi nítorí pé ọwọ́ mi mọ́.*+

21 Nítorí mo ti pa àwọn ọ̀nà Jèhófà mọ́,

Mi ò hùwà burúkú, kí n wá fi Ọlọ́run mi sílẹ̀.

22 Gbogbo ìdájọ́ rẹ̀ wà ní iwájú mi;

Mi ò ní pa àwọn òfin rẹ̀ tì.

23 Màá jẹ́ aláìlẹ́bi níwájú rẹ̀,+

Màá sì pa ara mi mọ́ kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀.+

24 Kí Jèhófà san èrè fún mi nítorí òdodo mi+

Àti nítorí pé ọwọ́ mi mọ́ ní iwájú rẹ̀.+

25 Ìwọ jẹ́ adúróṣinṣin sí ẹni tó jẹ́ adúróṣinṣin;+

Ìwọ ń hùwà àìlẹ́bi sí ọkùnrin aláìlẹ́bi;+

 26 Ìwọ jẹ́ mímọ́ sí ẹni tí ó mọ́,+

Àmọ́ ìwọ ń jẹ́ kí àwọn oníbékebèke mọ̀ pé òmùgọ̀ ni wọ́n.+

27 Ò ń gba àwọn ẹni rírẹlẹ̀* là+

Ṣùgbọ́n ò ń rẹ àwọn agbéraga*+ wálẹ̀.

28 Jèhófà, ìwọ lò ń tan fìtílà mi,

Ọlọ́run mi tó ń tan ìmọ́lẹ̀ sí òkùnkùn+ mi.

29 Ìrànlọ́wọ́ rẹ ni mo fi lè gbéjà ko àwọn jàǹdùkú;*+

Agbára Ọlọ́run ni mo fi lè gun ògiri.+

30 Pípé ni ọ̀nà Ọlọ́run tòótọ́;+

Ọ̀rọ̀ Jèhófà jẹ́ èyí tí a yọ́ mọ́.+

Apata ló jẹ́ fún gbogbo àwọn tó fi í ṣe ibi ààbò.+

31 Ta ni Ọlọ́run bí kò ṣe Jèhófà?+

Ta sì ni àpáta bí kò ṣe Ọlọ́run wa?+

32 Ọlọ́run tòótọ́ ni ẹni tó ń gbé agbára wọ̀ mí,+

Yóò sì mú kí ọ̀nà mi jẹ́ pípé.+

33 Ó ṣe ẹsẹ̀ mi bíi ti àgbọ̀nrín,

Ó sì mú mi dúró ní àwọn ibi gíga.+

34 Ó ń kọ́ ọwọ́ mi ní ogun,

Apá mi sì lè tẹ ọrun tí a fi bàbà ṣe.

35 O fún mi ní apata rẹ láti gbà mí là,+

Ọwọ́ ọ̀tún rẹ ń tì mí lẹ́yìn,*

Ìrẹ̀lẹ̀ rẹ sì sọ mí di ẹni ńlá.+

36 O fẹ ọ̀nà fún ẹsẹ̀ mi;

Kí ẹsẹ̀* mi má bàa yọ̀.+

37 Màá lépa àwọn ọ̀tá mi, màá sì bá wọn;

Mi ò ní pa dà títí wọ́n á fi pa rẹ́.

38 Màá fọ́ wọn túútúú, kí wọ́n má lè gbérí mọ́;+

Wọ́n á ṣubú sábẹ́ ẹsẹ̀ mi.

39 Wàá fún mi lókun láti jagun,

Wàá sì mú kí àwọn ọ̀tá mi ṣubú sábẹ́ mi.+

40 Wàá mú kí àwọn ọ̀tá mi pa dà lẹ́yìn mi,*

Màá sì pa àwọn tó kórìíra mi run.*+

41 Wọ́n kígbe fún ìrànlọ́wọ́, àmọ́ kò sí ẹni tó máa gbà wọ́n;

Kódà, wọ́n ké pe Jèhófà, àmọ́ kò dá wọn lóhùn.

42 Màá gún wọn kúnná bí eruku inú ẹ̀fúùfù,

Màá sì dà wọ́n nù bí ẹrẹ̀ ojú ọ̀nà.

43 Wàá gbà mí lọ́wọ́ àwọn èèyàn tó ń wá àléébù.+

Wàá yàn mí ṣe olórí àwọn orílẹ̀-èdè.+

Àwọn èèyàn tí mi ò mọ̀ yóò sìn mí.+

44 Ohun tí wọ́n bá gbọ́ nìkan yóò mú kí wọ́n ṣègbọràn sí mi;

Àwọn àjèjì á wá ba búrúbúrú níwájú mi.+

45 Ọkàn àwọn àjèjì á domi;*

Wọ́n á jáde tẹ̀rùtẹ̀rù látinú ibi ààbò wọn.

46 Jèhófà wà láàyè! Ìyìn ni fún Àpáta mi!+

Kí a gbé Ọlọ́run ìgbàlà mi ga.+

47 Ọlọ́run tòótọ́ ń gbẹ̀san fún mi;+

Ó ń ṣẹ́gun àwọn èèyàn lábẹ́ mi.

48 Ó ń gbà mí lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá mi tí inú ń bí;

Ìwọ gbé mi lékè àwọn tó ń gbéjà kò mí;+

O gbà mí lọ́wọ́ oníwà ipá.

49 Jèhófà, ìdí nìyẹn tí màá fi yìn ọ́ lógo láàárín àwọn orílẹ̀-èdè,+

Màá sì fi orin yin* orúkọ rẹ.+

50 Ó ń ṣe àwọn iṣẹ́ ìgbàlà* ńlá fún ọba rẹ̀;+

Ó ní ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ sí ẹni àmì òróró rẹ̀,+

Sí Dáfídì àti àtọmọdọ́mọ* rẹ̀ títí láé.+

Sí olùdarí. Orin Dáfídì.

19 Àwọn ọ̀run ń polongo ògo Ọlọ́run;+

Ojú ọ̀run* sì ń kéde iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀.+

 2 Láti ọjọ́ dé ọjọ́, ọ̀rọ̀ wọn ń tú jáde,

Láti òru dé òru, wọ́n ń fi ìmọ̀ hàn.

 3 Wọn kò fọhùn, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò sọ̀rọ̀;

A kò gbọ́ ohùn wọn.

 4 Síbẹ̀ ohùn wọn ti dún* jáde lọ sí gbogbo ayé,

Iṣẹ́ tí wọ́n ń jẹ́ sì ti dé ìkángun ilẹ̀ ayé tí à ń gbé.*+

Ọlọ́run ti pàgọ́ fún oòrùn sí ọ̀run;

 5 Ó dà bí ọkọ ìyàwó tó ń jáde bọ̀ látinú yàrá ìgbéyàwó;

Inú rẹ̀ ń dùn bí alágbára ọkùnrin tó ń sáré ní ipa ọ̀nà rẹ̀.

 6 Ó máa ń jáde láti ìkángun kan ọ̀run,

Á sì yí lọ dé ìkángun kejì;+

Kò sí nǹkan kan tó fara pa mọ́ kúrò nínú ooru rẹ̀.

 7 Òfin Jèhófà pé,+ ó ń sọ agbára dọ̀tun.*+

Ìránnilétí Jèhófà ṣeé gbẹ́kẹ̀ lé,+ ó ń sọ aláìmọ̀kan di ọlọ́gbọ́n.+

 8 Àwọn ìtọ́sọ́nà látọ̀dọ̀ Jèhófà jẹ́ òdodo, wọ́n ń mú ọkàn yọ̀;+

Àṣẹ Jèhófà mọ́, ó ń mú kí ojú mọ́lẹ̀.+

 9 Ìbẹ̀rù Jèhófà+ mọ́, ó wà títí láé.

Àwọn ìdájọ́ Jèhófà jẹ́ òótọ́, òdodo ni wọ́n látòkè délẹ̀.+

10 Wọ́n yẹ ní fífẹ́ ju wúrà,

Ju ọ̀pọ̀ wúrà tó dáa,*+

Wọ́n sì dùn ju oyin lọ,+ oyin inú afárá.

11 A ti fi wọ́n kìlọ̀ fún ìránṣẹ́ rẹ;+

Èrè ńlá wà nínú pípa wọ́n mọ́.+

12 Ta ló lè mọ àwọn àṣìṣe?+

Wẹ̀ mí mọ́ kúrò nínú àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tí mi ò mọ̀ nípa rẹ̀.

13 Má ṣe jẹ́ kí ìránṣẹ́ rẹ hùwà ògbójú;+

Má ṣe jẹ́ kí ó jọba lé mi lórí.+

Nígbà náà, màá pé pérépéré,+

Ọwọ́ mi á sì mọ́ nínú àwọn ẹ̀ṣẹ̀ ńlá.*

14 Kí ọ̀rọ̀ ẹnu mi àti àṣàrò ọkàn mi

Máa múnú rẹ dùn,+ Jèhófà, Àpáta mi+ àti Olùràpadà mi.+

Sí olùdarí. Orin Dáfídì.

20 Kí Jèhófà dá ọ lóhùn ní ọjọ́ wàhálà.

Kí orúkọ Ọlọ́run Jékọ́bù dáàbò bò ọ́.+

 2 Kó ràn ọ́ lọ́wọ́ láti ibi mímọ́,+

Kó sì gbé ọ ró láti Síónì.+

 3 Kó rántí gbogbo ọrẹ ẹ̀bùn rẹ;

Kó fi ojú rere gba ẹbọ sísun rẹ.* (Sélà)

 4 Kó fún ọ ní ohun tí ọkàn rẹ fẹ́,+

Kó sì mú kí gbogbo èrò* rẹ ṣẹ.

 5 A ó kígbe ayọ̀ nítorí àwọn iṣẹ́ ìgbàlà rẹ;+

A ó gbé àwọn ọ̀págun wa sókè ní orúkọ Ọlọ́run wa.+

Kí Jèhófà dáhùn gbogbo ohun tí o béèrè.

 6 Mo ti wá mọ̀ pé Jèhófà ń gba ẹni àmì òróró rẹ̀ sílẹ̀.+

Ó ń dá a lóhùn láti ọ̀run mímọ́

Pẹ̀lú ìgbàlà* ńlá ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀.+

 7 Àwọn kan gbẹ́kẹ̀ lé kẹ̀kẹ́ ẹṣin, àwọn míì sì gbẹ́kẹ̀ lé ẹṣin,+

Àmọ́, àwa ń ké pe orúkọ Jèhófà Ọlọ́run wa.+

 8 Wọ́n ti kọsẹ̀, wọ́n sì ti ṣubú lulẹ̀,

Àmọ́ àwa ti dìde, a sì ti kọ́fẹ pa dà.+

 9 Jèhófà, gba ọba sílẹ̀!+

Yóò dá wa lóhùn ní ọjọ́ tí a bá ké pè é fún ìrànlọ́wọ́.+

Sí olùdarí. Orin Dáfídì.

21 Jèhófà, inú agbára rẹ ni ọba ti ń yọ̀;+

Wo bí ó ṣe ń yọ̀ gidigidi nínú àwọn iṣẹ́ ìgbàlà rẹ!+

 2 O ti fún un ní ohun tí ọkàn rẹ̀ fẹ́,+

Ìwọ kò sì fi ohun tó béèrè dù ú. (Sélà)

 3 Nítorí pé o fi ọ̀pọ̀ ìbùkún pàdé rẹ̀;

O fi adé wúrà tó dáa* dé e ní orí.+

 4 Ó béèrè ẹ̀mí lọ́wọ́ rẹ, o sì fún un,+

Ẹ̀mí gígùn,* títí láé àti láéláé.

 5 Àwọn iṣẹ́ ìgbàlà rẹ fún un ní ògo ńlá.+

O fi iyì àti ọlá jíǹkí rẹ̀.

 6 O sọ ọ́ di ẹni ìbùkún títí láé;+

O mú kí ó máa yọ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀ nítorí o* wà pẹ̀lú rẹ̀.+

 7 Ọba gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà;+

Nítorí ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ tí Ẹni Gíga Jù Lọ ní, mìmì kan ò ní mì í* láé.+

 8 Ọwọ́ rẹ á tẹ gbogbo àwọn ọ̀tá rẹ;

Ọwọ́ ọ̀tún rẹ á tẹ àwọn tó kórìíra rẹ.

 9 Wàá ṣe wọ́n bí ohun tí a jù sínú iná ìléru ní àkókò tí o yàn láti fiyè sí wọn.

Jèhófà máa gbé wọn mì nínú ìbínú rẹ̀, iná á sì jó wọn run.+

10 Wàá pa àtọmọdọ́mọ* wọn run kúrò ní ayé,

Àti ọmọ wọn kúrò láàárín àwọn ọmọ èèyàn.

11 Wọ́n fẹ́ ṣe ohun tí kò dáa sí ọ;+

Wọ́n ti gbèrò ibi, àmọ́ kò ní ṣẹ.+

12 Wàá mú kí wọ́n sá pa dà+

Nígbà tí o bá dojú ọfà* rẹ kọ wọ́n.*

13 Dìde nínú agbára rẹ, Jèhófà.

A ó fi orin yin* agbára ńlá rẹ.

Sí olùdarí; kí a yí i sí “Egbin Àfẹ̀mọ́jú.”* Orin Dáfídì.

22 Ọlọ́run mi, Ọlọ́run mi, kí ló dé tí o fi kọ̀ mí sílẹ̀?+

Kí nìdí tí o fi jìnnà sí mi láti gbà mí sílẹ̀,

Tí o sì jìnnà sí igbe ìrora mi?+

 2 Ọlọ́run mi, mò ń ké pè ọ́ ní ọ̀sán, àmọ́ o ò dáhùn;+

Kódà ní òru, mi ò dákẹ́.

 3 Àmọ́ ẹni mímọ́+ ni ọ́,

Ìyìn Ísírẹ́lì sì yí ọ ká.*

 4 Ìwọ ni àwọn baba wa gbẹ́kẹ̀ lé;+

Wọ́n gbẹ́kẹ̀ lé ọ, o sì ń gbà wọ́n sílẹ̀.+

 5 Ìwọ ni wọ́n ké pè, o sì gbà wọ́n;

Wọ́n gbẹ́kẹ̀ lé ọ, o ò sì já wọn kulẹ̀.*+

 6 Àmọ́ kòkòrò mùkúlú ni mí, èmi kì í ṣe èèyàn,

Àwọn èèyàn ń fi mí ṣẹ̀sín,* aráyé ò sì kà mí sí.+

 7 Gbogbo àwọn tó ń rí mi ló ń fi mí ṣe yẹ̀yẹ́;+

Wọ́n ń yínmú, wọ́n sì ń mi orí wọn, pé:+

 8 “Ó fi ara rẹ̀ lé Jèhófà lọ́wọ́. Kí Ó gbà á sílẹ̀ báyìí!

Kí Ó gbà á là, ṣebí ó fẹ́ràn Rẹ̀ gan-an!”+

 9 Ìwọ ni Ó gbé mi jáde láti inú ìyá mi,+

Ìwọ ni O mú kí ọkàn mi balẹ̀ ní àyà ìyá mi.

10 Ọwọ́ rẹ ni mo wà* látìgbà tí wọ́n ti bí mi;

Ìwọ ni Ọlọ́run mi láti inú ìyá mi wá.

11 Má jìnnà sí mi, torí wàhálà ti dé tán+

Mi ò sì ní olùrànlọ́wọ́+ míì.

12 Ọ̀pọ̀ akọ ọmọ màlúù yí mi ká;+

Àwọn akọ màlúù Báṣánì tó lágbára rọ̀gbà yí mi ká.+

13 Wọ́n ya ẹnu wọn sí mi,+

Bíi kìnnìún tó ń ké ramúramù, tó sì ń fa ẹran ya.+

14 A tú mi jáde bí omi;

Gbogbo egungun mi ti yẹ̀.

Ọkàn mi ti dà bí ìda;+

Ó yọ́ nínú mi lọ́hùn-ún.+

15 Okun mi ti tán, mo dà bí èéfọ́ ìkòkò;+

Ahọ́n mi lẹ̀ mọ́ ẹran ìdí eyín mi;+

O sì mú mi wálẹ̀ sínú ekuru kí n lè kú.+

16 Nítorí àwọn ajá yí mi ká;+

Wọ́n ká mi mọ́ bí ìgbà tí àwọn aṣebi bá káni mọ́,+

Wọ́n wà níbi ọwọ́ àti ẹsẹ̀ mi bíi kìnnìún.+

17 Mo lè ka gbogbo egungun mi.+

Wọ́n ń wò mí, wọ́n sì tẹjú mọ́ mi.

18 Wọ́n pín ẹ̀wù mi láàárín ara wọn,

Wọ́n sì ṣẹ́ kèké nítorí aṣọ mi.+

19 Àmọ́ ìwọ, Jèhófà, má jìnnà sí mi.+

Ìwọ ni okun mi; tètè wá ràn mí lọ́wọ́.+

20 Gbà mí* lọ́wọ́ idà,

Gba ẹ̀mí mi tó ṣeyebíye* lọ́wọ́ èékánná* ajá;+

 21 Gbà mí kúrò lẹ́nu kìnnìún  + àti lọ́wọ́ ìwo akọ màlúù igbó;

Dá mi lóhùn, kí o sì gbà mí sílẹ̀.

22 Màá sọ orúkọ rẹ fún àwọn arákùnrin mi;+

Màá sì yìn ọ́ láàárín ìjọ.+

23 Ẹ̀yin tí ẹ bẹ̀rù Jèhófà, ẹ yìn ín!

Gbogbo ẹ̀yin ọmọ* Jékọ́bù, ẹ yìn ín lógo!+

Ẹ máa bẹ̀rù rẹ̀, gbogbo ẹ̀yin ọmọ* Ísírẹ́lì.

24 Nítorí kò gbójú fo ìyà tó ń jẹ ẹni tí ara ń ni, kò sì ṣàìka ìpọ́njú rẹ̀ sí;+

Kò gbé ojú rẹ̀ pa mọ́ fún un.+

Nígbà tó ké pè é fún ìrànlọ́wọ́, ó gbọ́.+

25 Màá yìn ọ́ láàárín ìjọ ńlá;+

Màá san àwọn ẹ̀jẹ́ mi níwájú àwọn tó bẹ̀rù rẹ.

26 Àwọn oníwà pẹ̀lẹ́ á jẹ, wọ́n á sì yó;+

Àwọn tó ń wá Jèhófà yóò yìn ín.+

Kí wọ́n gbádùn ayé* títí láé.

27 Gbogbo ayé á rántí, wọ́n á sì yíjú sọ́dọ̀ Jèhófà.

Gbogbo ìdílé àwọn orílẹ̀-èdè á tẹrí ba níwájú rẹ.+

28 Nítorí pé ti Jèhófà ni ìjọba;+

Ó ń ṣàkóso àwọn orílẹ̀-èdè.

29 Gbogbo àwọn tó láásìkí* nínú ayé á jẹ, wọ́n á sì tẹrí ba;

Gbogbo àwọn tó ń lọ sínú erùpẹ̀ yóò wólẹ̀ níwájú rẹ̀;

Kò sí ìkankan lára wọn tó lè dá ẹ̀mí* rẹ̀ sí.

30 Àwọn àtọmọdọ́mọ wọn* yóò máa sìn ín;

Ìran tó ń bọ̀ yóò gbọ́ nípa Jèhófà.

31 Wọ́n á wá, wọ́n á sì sọ nípa òdodo rẹ̀.

Wọ́n á sọ fún àwọn ọmọ tí a máa bí nípa ohun tó ṣe.

Orin Dáfídì.

23 Jèhófà ni Olùṣọ́ Àgùntàn mi.+

Èmi kì yóò ṣaláìní.+

 2 Ó mú mi dùbúlẹ̀ ní ibi ìjẹko tútù;

Ó darí mi sí àwọn ibi ìsinmi tó lómi dáadáa.*+

 3 Ó tù mí* lára.+

Ó darí mi ní ipa ọ̀nà òdodo nítorí orúkọ rẹ̀.+

 4 Bí mo tilẹ̀ ń rìn nínú àfonífojì tó ṣókùnkùn biribiri,+

Mi ò bẹ̀rù ewukéwu,+

Nítorí o wà pẹ̀lú mi;+

Ọ̀gọ* rẹ àti ọ̀pá rẹ ń fi mí lọ́kàn balẹ̀.*

 5 O tẹ́ tábìlì fún mi níwájú àwọn ọ̀tá mi.+

O fi òróró pa orí mi;*+

Ife mi kún dáadáa.+

 6 Dájúdájú, ire àti ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ yóò máa tọ̀ mí lẹ́yìn ní gbogbo ọjọ́ ayé mi,+

Èmi yóò sì máa gbé inú ilé Jèhófà ní gbogbo ọjọ́ ayé mi.+

Ti Dáfídì. Orin.

24 Jèhófà ló ni ayé àti gbogbo ohun tó wà nínú rẹ̀,+

Ilẹ̀ tó ń méso jáde àti àwọn tó ń gbé orí rẹ̀.

 2 Nítorí ó ti fìdí rẹ̀ sọlẹ̀ sórí òkun+

Ó sì fìdí rẹ̀ múlẹ̀ sórí àwọn odò.

 3 Ta ló lè gun orí òkè Jèhófà,+

Ta ló sì lè dúró ní ibi mímọ́ rẹ̀?

 4 Ẹni tí ọwọ́ rẹ̀ mọ́, tí ọkàn rẹ̀ sì mọ́,+

Ẹni tí kò fi ẹ̀mí Mi* búra èké,

Tí kò sì búra ẹ̀tàn.+

 5 Yóò gba ìbùkún látọ̀dọ̀ Jèhófà+

Àti òdodo* látọ̀dọ̀ Ọlọ́run ìgbàlà rẹ̀.+

 6 Ìran àwọn tó ń wá a nìyí,

Ti àwọn tó ń wá ojú rẹ, ìwọ Ọlọ́run Jékọ́bù. (Sélà)

 7 Ẹ gbé orí yín sókè, ẹ̀yin ẹnubodè;+

Ẹ ṣí sílẹ̀,* ẹ̀yin ẹnu ọ̀nà àtijọ́,

Kí Ọba ológo lè wọlé!+

 8 Ta ni Ọba ológo yìí?

Jèhófà ni, ẹni tó ní okun àti agbára,+

Jèhófà, akin lójú ogun.+

 9 Ẹ gbé orí yín sókè, ẹ̀yin ẹnubodè;+

Ẹ ṣí sílẹ̀, ẹ̀yin ẹnu ọ̀nà àtijọ́,

Kí Ọba ológo lè wọlé!

10 Ta ni Ọba ológo yìí?

Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun ni, òun ni Ọba ológo náà.+ (Sélà)

Ti Dáfídì.

א [Áléfì]

25 Jèhófà, ọ̀dọ̀ rẹ ni mo yíjú* sí.

ב [Bétì]

 2 Ọlọ́run mi, ìwọ ni mo gbẹ́kẹ̀ lé;+

Má ṣe jẹ́ kí ojú tì mí.+

Má ṣe jẹ́ kí àwọn ọ̀tá mi yọ̀ mí.+

ג [Gímélì]

 3 Ó dájú pé ojú ò ní ti ìkankan nínú àwọn tó nírètí nínú rẹ,+

Àmọ́ ojú á ti àwọn tó jẹ́ oníbékebèke láìnídìí.+

ד [Dálétì]

 4 Mú mi mọ àwọn ọ̀nà rẹ, Jèhófà;+

Kọ́ mi ní àwọn ipa ọ̀nà rẹ.+

ה [Híì]

 5 Mú kí n máa rìn nínú òtítọ́ rẹ, kí o sì kọ́ mi,+

Nítorí ìwọ ni Ọlọ́run ìgbàlà mi.

ו [Wọ́ọ̀]

Ìwọ ni mo gbẹ́kẹ̀ lé láti àárọ̀ ṣúlẹ̀.

ז [Sáyìn]

 6 Jèhófà, rántí àánú rẹ àti ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀,+

Èyí tí ò ń fi hàn nígbà gbogbo.*+

ח [Hétì]

 7 Má ṣe rántí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ ìgbà èwe mi àti àwọn àṣìṣe mi.

Rántí mi nínú ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀,+

Nítorí oore rẹ, Jèhófà.+

ט [Tétì]

 8 Ẹni rere àti adúróṣinṣin ni Jèhófà.+

Ìdí nìyẹn tó fi ń kọ́ àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ ní ọ̀nà tó yẹ kí wọ́n tọ̀.+

י [Yódì]

 9 Yóò darí àwọn oníwà pẹ̀lẹ́ láti ṣe ohun tí ó tọ́,*+

Yóò sì kọ́ àwọn oníwà pẹ̀lẹ́ ní ọ̀nà rẹ̀.+

כ [Káfì]

10 Gbogbo ọ̀nà Jèhófà jẹ́ ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ àti òtítọ́

Fún àwọn tó ń pa májẹ̀mú rẹ̀+ àti àwọn ìránnilétí+ rẹ̀ mọ́.

ל [Lámédì]

11 Nítorí orúkọ rẹ, Jèhófà,+

Dárí ẹ̀ṣẹ̀ mi jì mí, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó pọ̀.

מ [Mémì]

12 Ta ni ẹni tó ń bẹ̀rù Jèhófà?+

Òun yóò kọ́ ẹni náà ní ọ̀nà tó yẹ kí ó yàn.+

נ [Núnì]

13 Yóò* gbádùn ohun rere,+

Àwọn àtọmọdọ́mọ* rẹ̀ yóò sì jogún ayé.+

ס [Sámékì]

14 Àwọn tó bẹ̀rù Jèhófà ni ọ̀rẹ́ rẹ̀ tímọ́tímọ́,+

Ó sì ń jẹ́ kí wọ́n mọ májẹ̀mú rẹ̀.+

ע [Áyìn]

15 Ọ̀dọ̀ Jèhófà ni ojú mi ń wò nígbà gbogbo,+

Nítorí ó máa yọ ẹsẹ̀ mi nínú àwọ̀n.+

פ [Péè]

16 Bojú wò mí, kí o sì ṣojú rere sí mi,

Nítorí mo dá wà, mi ò sì ní olùrànlọ́wọ́.

צ [Sádì]

17 Ìdààmú ọkàn mi ti pọ̀ sí i;+

Yọ mí nínú másùnmáwo tó bá mi.

ר [Réṣì]

18 Wo ìpọ́njú mi àti wàhálà mi,+

Kí o sì dárí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ mi jì mí.+

19 Wo bí àwọn ọ̀tá mi ṣe pọ̀ tó,

Àti bí ìkórìíra tí wọ́n ní sí mi ṣe lágbára tó.

ש [Ṣínì]

 20 Ṣọ́ ẹ̀mí* mi, kí o sì gbà mí sílẹ̀.+

Má ṣe jẹ́ kí ojú tì mí, nítorí ìwọ ni mo fi ṣe ibi ààbò mi.

ת [Tọ́ọ̀]

 21 Kí ìwà títọ́ àti ìdúróṣinṣin máa dáàbò bò mí,+

Nítorí ìwọ ni mo gbẹ́kẹ̀ lé.+

 22 Ọlọ́run, gba Ísírẹ́lì kúrò* nínú gbogbo wàhálà rẹ̀.

Ti Dáfídì.

26 Ṣe ìdájọ́ mi, Jèhófà, nítorí mo ti rìn nínú ìwà títọ́ mi;+

Jèhófà ni mo gbẹ́kẹ̀ lé láìmikàn.+

 2 Yẹ̀ mí wò, Jèhófà, kí o sì dán mi wò;

Yọ́ èrò inú mi* àti ọkàn mi mọ́.+

 3 Nítorí ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ máa ń wà níwájú mi nígbà gbogbo,

Mo sì ń rìn nínú òtítọ́ rẹ.+

 4 Èmi kì í bá àwọn ẹlẹ́tàn kẹ́gbẹ́,*+

Mo sì máa ń yẹra fún àwọn tó ń fi ẹni tí wọ́n jẹ́ pa mọ́.*

 5 Mo kórìíra àwùjọ àwọn aṣebi,+

Mi ò sì jẹ́ bá àwọn ẹni burúkú kẹ́gbẹ́.*+

 6 Màá jẹ́ kí ọwọ́ mi mọ́,

Màá sì rìn yí ká pẹpẹ rẹ, Jèhófà,

 7 Láti mú kí a gbọ́ ohùn ọpẹ́+

Àti láti kéde gbogbo iṣẹ́ àgbàyanu rẹ.

 8 Jèhófà, mo nífẹ̀ẹ́ ilé tí ò ń gbé,+

Ibi tí ògo rẹ wà.+

 9 Má ṣe gbá mi* dà nù pẹ̀lú àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀+

Má sì gba ẹ̀mí mi pẹ̀lú àwọn oníwà ipá,*

10 Àwọn tó ń lọ́wọ́ nínú ìwà àìnítìjú,

Tí àbẹ̀tẹ́lẹ̀ sì kún ọwọ́ ọ̀tún wọn.

11 Àmọ́ ní tèmi, èmi yóò máa rìn nínú ìwà títọ́ mi.

Gbà mí sílẹ̀,* kí o sì ṣojú rere sí mi.

12 Ẹsẹ̀ mi dúró lórí ilẹ̀ tó tẹ́jú;+

Nínú ìjọ ńlá,* èmi yóò yin Jèhófà.+

Ti Dáfídì.

27 Jèhófà ni ìmọ́lẹ̀ mi+ àti ìgbàlà mi.

Ta ni èmi yóò bẹ̀rù?+

Jèhófà ni odi ààbò ayé mi.+

Ta ni èmi yóò fòyà?

 2 Nígbà tí àwọn ẹni ibi gbéjà kò mí láti jẹ ẹran ara mi,+

Àwọn elénìní mi àti àwọn ọ̀tá mi ló kọsẹ̀ tí wọ́n sì ṣubú.

 3 Bí àwọn ọmọ ogun tilẹ̀ pàgọ́ tì mí,

Ọkàn mi kò ní bẹ̀rù.+

Bí ogun tilẹ̀ dìde sí mi,

Síbẹ̀, mi ò ní mikàn.

 4 Ohun kan ni mo béèrè lọ́wọ́ Jèhófà,

Òun ni mo sì ń wá, pé:

Kí n máa gbé inú ilé Jèhófà ní gbogbo ọjọ́ ayé mi,+

Kí n máa rí adùn Jèhófà,

Kí n sì máa fi ìmọrírì* wo tẹ́ńpìlì* rẹ̀.+

 5 Nítorí yóò fi mí pa mọ́ sí ibi kọ́lọ́fín rẹ̀ ní ọjọ́ àjálù;+

Yóò tọ́jú mi pa mọ́ sí ibi ìkọ̀kọ̀ àgọ́ rẹ̀;+

Yóò gbé mi sórí àpáta.+

 6 Báyìí, orí mi yọ sókè ju àwọn ọ̀tá mi tó yí mi ká;

Màá fi igbe ayọ̀ rú àwọn ẹbọ ní àgọ́ rẹ̀;

Màá fi orin yin* Jèhófà.

 7 Fetí sí mi, Jèhófà, nígbà tí mo bá ké pè ọ́;+

Ṣojú rere sí mi, kí o sì dá mi lóhùn.+

 8 Ọkàn mi gbẹnu sọ fún ọ, ó ní:

“Wá ọ̀nà láti rí ojú mi.”

Jèhófà, èmi yóò wá ọ̀nà láti rí ojú rẹ.+

 9 Má fi ojú rẹ pa mọ́ fún mi.+

Má fi ìbínú lé ìránṣẹ́ rẹ kúrò.

Ìwọ ni olùrànlọ́wọ́ mi;+

Má pa mí tì, má sì fi mí sílẹ̀, Ọlọ́run ìgbàlà mi.

10 Kódà, tí bàbá mi àti ìyá mi bá kọ̀ mí sílẹ̀,+

Jèhófà fúnra rẹ̀ yóò tẹ́wọ́ gbà mí.+

11 Jèhófà, kọ́ mi ní ọ̀nà rẹ,+

Darí mi ní ọ̀nà ìdúróṣinṣin nítorí àwọn ọ̀tá mi.

12 Má fi mí lé ọwọ́ àwọn elénìní mi,*+

Nítorí pé àwọn ẹlẹ́rìí èké ti dìde sí mi,+

Wọ́n sì ń halẹ̀ pé àwọn máa ṣe mí léṣe.

13 Ibo ni mi ò bá wà, ká ní mi ò ní ìgbàgbọ́

Pé màá rí oore Jèhófà ní ilẹ̀ alààyè?*+

14 Gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà;+

Ní ìgboyà, kí o sì mọ́kàn le.+

Bẹ́ẹ̀ ni, gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà.

Ti Dáfídì.

28 Ìwọ ni mò ń ké pè, Jèhófà, Àpáta+ mi;

Má di etí rẹ sí mi.

Tí o ò bá dá mi lóhùn,

Ṣe ni màá dà bí àwọn tó ń lọ sínú kòtò.*+

 2 Gbọ́ ẹ̀bẹ̀ mi nígbà tí mo bá ké pè ọ́ fún ìrànlọ́wọ́

Bí mo ṣe ń gbé ọwọ́ mi sókè sí yàrá inú lọ́hùn-ún ti ibi mímọ́ rẹ.+

 3 Má ṣe fà mí lọ pẹ̀lú àwọn ẹni ibi, pẹ̀lú àwọn tó ń ṣe ohun búburú,+

Àwọn tó ń bá ọmọnìkejì wọn sọ̀rọ̀ àlàáfíà, àmọ́ tó jẹ́ pé ibi ló wà lọ́kàn wọn.+

 4 San ohun tí wọ́n ṣe pa dà fún wọn,+

Gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ ibi wọn.

San iṣẹ́ ọwọ́ wọn pa dà fún wọn,

Gẹ́gẹ́ bí ohun tí wọ́n ṣe.+

 5 Nítorí pé wọn kò fiyè sí àwọn iṣẹ́ Jèhófà,+

Wọn ò sì ka iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀ sí.+

Yóò ya wọ́n lulẹ̀, kò sì ní gbé wọn ró.

 6 Ìyìn ni fún Jèhófà,

Torí ó ti gbọ́ ẹ̀bẹ̀ mi fún ìrànlọ́wọ́.

 7 Jèhófà ni agbára mi+ àti apata mi;+

Òun ni ọkàn mi gbẹ́kẹ̀ lé.+

Ó ti ràn mí lọ́wọ́, ọkàn mi sì ń yọ̀,

Torí náà, màá fi orin mi yìn ín.

 8 Jèhófà ni agbára àwọn èèyàn rẹ̀;

Ó jẹ́ ibi ààbò, ó ń fún ẹni àmì òróró rẹ̀ ní ìgbàlà ńlá.+

 9 Gba àwọn èèyàn rẹ là, kí o sì bù kún ogún rẹ.+

Máa ṣe olùṣọ́ àgùntàn wọn, kí o sì gbé wọn sí apá rẹ títí láé.+

Orin Dáfídì.

29 Ẹ fún Jèhófà ní ohun tí ó tọ́ sí i, ẹ̀yin ọmọ àwọn alágbára,

Ẹ fún Jèhófà ní ohun tí ó tọ́ sí i nítorí ògo àti agbára rẹ̀.+

 2 Ẹ fún Jèhófà ní ògo tí ó yẹ orúkọ rẹ̀.

Ẹ forí balẹ̀ fún* Jèhófà nínú aṣọ ọ̀ṣọ́ mímọ́.*

 3 A gbọ́ ohùn Jèhófà lórí omi;

Ọlọ́run ológo sán ààrá.+

Jèhófà wà lórí omi púpọ̀.+

 4 Ohùn Jèhófà ní agbára;+

Ohùn Jèhófà ní ọlá ńlá.

 5 Ohùn Jèhófà ń fa àwọn igi kédárì ya;

Bẹ́ẹ̀ ni, Jèhófà ń fa àwọn igi kédárì Lẹ́bánónì+ ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ.

 6 Ó ń mú kí Lẹ́bánónì* máa ta pọ́n-ún pọ́n-ún bí ọmọ màlúù

Àti Síríónì+ bí akọ ọmọ màlúù igbó.

 7 Ohùn Jèhófà ń mú kí mànàmáná kọ;+

 8 Ohùn Jèhófà ń mú kí aginjù mì tìtì;+

Jèhófà ń mú kí aginjù Kádéṣì+ mì tìtì.

 9 Ohùn Jèhófà kó jìnnìjìnnì bá àwọn àgbọ̀nrín, wọ́n sì bímọ,

Bákan náà, ó ń tú àwọn igbó kìjikìji sí borokoto.+

Gbogbo àwọn tó wà nínú tẹ́ńpìlì rẹ̀ sì sọ pé: “Ògo!”

10 Jèhófà gúnwà sórí ìkún omi;*+

Jèhófà gúnwà bí Ọba títí láé.+

11 Jèhófà yóò fún àwọn èèyàn rẹ̀ ní agbára.+

Jèhófà yóò fi àlàáfíà jíǹkí àwọn èèyàn rẹ̀.+

Orin. Orin ìṣílé. Ti Dáfídì.

30 Màá gbé ọ ga, Jèhófà, nítorí o ti gbé mi* sókè,

O ò jẹ́ kí àwọn ọ̀tá mi yọ̀ mí.+

 2 Jèhófà Ọlọ́run mi, mo ké pè ọ́ fún ìrànlọ́wọ́, o sì wò mí sàn.+

 3 Jèhófà, o ti gbé mi* sókè látinú Isà Òkú.*+

O mú kí n wà láàyè, o ò sì jẹ́ kí n rì sínú kòtò.*+

 4 Ẹ fi orin yin* Jèhófà, ẹ̀yin ẹni ìdúróṣinṣin rẹ̀,+

Ẹ fi ọpẹ́ fún orúkọ* mímọ́ rẹ̀;+

 5 Nítorí ìbínú rẹ̀ lórí èèyàn kì í pẹ́ rárá,+

Àmọ́ ojú rere* rẹ̀ sí èèyàn wà títí ọjọ́ ayé.+

Ẹkún lè wà ní àṣálẹ́, àmọ́ tó bá di àárọ̀, igbe ayọ̀ á sọ.+

 6 Nígbà tí kò sí ìdààmú kankan fún mi, mo sọ pé:

“Mìmì kan ò ní mì mí.”*

 7 Jèhófà, nígbà tí o ṣojú rere sí mi,* o mú kí n lágbára bí òkè.+

Àmọ́ nígbà tí o fi ojú rẹ pa mọ́, jìnnìjìnnì bá mi.+

 8 Jèhófà, ìwọ ni mò ń ké pè;+

Jèhófà ni mo sì ń bẹ̀ fún ojú rere.

 9 Èrè wo ló wà nínú ikú* mi, nínú bí mo ṣe ń lọ sínú kòtò?*+

Ṣé erùpẹ̀ lè yìn ọ́?+ Ṣé ó lè sọ nípa ìṣòtítọ́ rẹ?+

10 Fetí sílẹ̀, Jèhófà, kí o sì ṣojú rere sí mi.+

Jèhófà, wá ràn mí lọ́wọ́.+

11 O ti sọ ọ̀fọ̀ mi di ijó;

O ti bọ́ aṣọ ọ̀fọ̀* mi, o sì fi aṣọ ìdùnnú wọ̀ mí,

12 Kí n* lè máa kọrin ìyìn rẹ, kí n má sì dákẹ́.

Jèhófà Ọlọ́run mi, èmi yóò máa yìn ọ́ títí láé.

Sí olùdarí. Orin Dáfídì.

31 Jèhófà, ìwọ ni mo fi ṣe ibi ààbò mi.+

Kí ojú má tì mí láé.+

Gbà mí sílẹ̀ nítorí òdodo rẹ.+

 2 Tẹ́tí sí mi.*

Tètè wá gbà mí sílẹ̀.+

Di àpáta ààbò fún mi,

Ibi olódi láti gbà mí sílẹ̀.+

 3 Ìwọ ni àpáta mi àti ibi ààbò mi;+

Wàá darí mi,+ wàá sì ṣamọ̀nà mi, nítorí orúkọ rẹ.+

 4 Wàá yọ mí kúrò nínú àwọ̀n tí wọ́n dẹ pa mọ́ dè mí,+

Nítorí pé ìwọ ni odi ààbò mi.+

 5 Ọwọ́ rẹ ni mo fi ẹ̀mí mi lé.+

O ti rà mí pa dà, Jèhófà, Ọlọ́run òtítọ́.*+

 6 Mo kórìíra àwọn tó ń bọ òrìṣà asán, tí kò ní láárí,

Àmọ́ ní tèmi, Jèhófà ni mo gbẹ́kẹ̀ lé.

 7 Ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ yóò máa mú inú mi dùn gidigidi,

Nítorí o ti rí ìpọ́njú mi;+

O mọ ìdààmú ńlá tó bá mi.*

 8 O kò fi mí lé ọ̀tá lọ́wọ́,

Àmọ́ o mú kí n dúró ní ibi ààbò.*

 9 Ṣojú rere sí mi, Jèhófà, torí mo wà nínú ìdààmú.

Ìrora ti sọ ojú mi di bàìbàì,+ àárẹ̀ sì ti bá gbogbo ara mi.*+

10 Ẹ̀dùn ọkàn+ ti gba ayé mi kan,

Ìrora ni mo sì fi ń lo ọdún ayé mi.+

Agbára mi ń tán lọ nítorí ẹ̀ṣẹ̀ mi;

Àárẹ̀ ti mú egungun mi.+

11 Gbogbo àwọn ọ̀tá mi ń fi mí ṣẹ̀sín,+

Pàápàá àwọn aládùúgbò mi.

Mo ti di ẹni àríbẹ̀rù lójú àwọn ojúlùmọ̀ mi;

Tí wọ́n bá rí mi lóde, ṣe ni wọ́n ń sá fún mi.+

12 Mi ò sí lọ́kàn wọn mọ́,* wọ́n sì ti gbàgbé mi, àfi bíi pé mo ti kú;

Mo dà bí ìkòkò tó fọ́.

13 Mo ti gbọ́ ọ̀pọ̀ àhesọ burúkú;

Àwọn ohun ẹ̀rù yí mi ká.+

Nígbà tí wọ́n kóra jọ lé mi lórí,

Wọ́n gbèrò láti gba ẹ̀mí* mi.+

14 Àmọ́ Jèhófà, ìwọ ni mo gbẹ́kẹ̀ lé.+

Mo sọ pé: “Ìwọ ni Ọlọ́run mi.”+

15 Ọwọ́ rẹ ni ọjọ́ ayé* mi wà.

Gbà mí lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá mi àti lọ́wọ́ àwọn tó ń ṣe inúnibíni sí mi.+

16 Mú kí ojú rẹ tàn sára ìránṣẹ́ rẹ.+

Fi ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ gbà mí sílẹ̀.

17 Jèhófà, kí ojú má tì mí nígbà tí mo bá ké pè ọ́.+

Kí ojú ti àwọn ẹni burúkú;+

Kí wọ́n dákẹ́ sínú Isà Òkú.*+

18 Kí kẹ́kẹ́ pa mọ́ àwọn òpùrọ́ lẹ́nu,+

Àwọn tó ń sọ̀rọ̀ ìgbéraga àti ẹ̀gàn sí àwọn olódodo.

19 Oore rẹ mà pọ̀ o!+

O ti tò wọ́n jọ fún àwọn tó bẹ̀rù rẹ,+

O sì ti fi wọ́n hàn lójú gbogbo èèyàn, nítorí àwọn tó fi ọ́ ṣe ibi ààbò.+

20 Wàá fi wọ́n pa mọ́ sí ibi ìkọ̀kọ̀ tó wà níwájú rẹ+

Kúrò nínú rìkíṣí àwọn èèyàn;

Wàá fi wọ́n pa mọ́ sínú àgọ́ rẹ

Kúrò lọ́wọ́ àwọn abanijẹ́.*+

21 Ìyìn ni fún Jèhófà,

Nítorí ó ti fi ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ hàn sí mi lọ́nà àgbàyanu+ ní ìlú tí ọ̀tá dó tì.+

22 Ní tèmi, jìnnìjìnnì bò mí, mo sì sọ pé:

“Màá ṣègbé níwájú rẹ.”+

Àmọ́ nígbà tí mo ké pè ọ́, o gbọ́ ẹ̀bẹ̀ mi fún ìrànlọ́wọ́.+

23 Ẹ nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, gbogbo ẹ̀yin tí ẹ jẹ́ adúróṣinṣin sí i!+

Jèhófà ń dáàbò bo àwọn olóòótọ́,+

Àmọ́ ó máa ń san èrè tó kún rẹ́rẹ́ fún àwọn tó bá ń gbéra ga.+

24 Ẹ jẹ́ onígboyà, kí ẹ sì mọ́kàn le,+

Gbogbo ẹ̀yin tí ẹ̀ ń dúró de Jèhófà.+

Ti Dáfídì. Másíkílì.*

32 Aláyọ̀ ni ẹni tí a dárí àṣìṣe rẹ̀ jì, tí a sì bo ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ mọ́lẹ̀.*+

 2 Aláyọ̀ ni ẹni tí Jèhófà kò ka ẹ̀bi sí lọ́rùn,+

Ẹni tí kò sí ẹ̀tàn nínú ẹ̀mí rẹ̀.

 3 Nígbà tí mo dákẹ́, egungun mi ń ṣàárẹ̀ torí mò ń kérora láti àárọ̀ ṣúlẹ̀.+

 4 Tọ̀sántòru ni ọwọ́* rẹ le lára mi.+

Okun mi ti gbẹ* bí omi ṣe ń gbẹ nígbà ẹ̀ẹ̀rùn. (Sélà)

 5 Níkẹyìn, mo jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ mi fún ọ;

Mi ò bo àṣìṣe mi mọ́lẹ̀.+

Mo sọ pé: “Màá jẹ́wọ́ àwọn ẹ̀ṣẹ̀ mi fún Jèhófà.”+

O sì dárí àṣìṣe àti ẹ̀ṣẹ̀ mi jì mí.+ (Sélà)

 6 Ìdí nìyí tí gbogbo adúróṣinṣin yóò máa gbàdúrà sí ọ+

Nígbà tí wọ́n ṣì lè rí ọ.+

Kódà nígbà náà, àkúnya omi kò ní dé ọ̀dọ̀ wọn.

 7 Ìwọ ni ibi ìfarapamọ́ mi;

Wàá dáàbò bò mí nínú wàhálà.+

Wàá fi igbe ayọ̀ ìgbàlà yí mi ká.+ (Sélà)

 8 “Màá fún ọ ní ìjìnlẹ̀ òye, màá sì kọ́ ọ ní ọ̀nà tó yẹ kí o máa rìn.+

Màá fún ọ ní ìmọ̀ràn pẹ̀lú ojú mi lára rẹ.+

 9 Ẹ má dà bí ẹṣin tàbí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́* tí kò ní òye,+

Tó jẹ́ pé ìjánu tàbí okùn la fi ń kì í wọ̀ tó bá ń ta pọ́n-ún pọ́n-ún

Kó tó lè sún mọ́ni.”

10 Ọ̀pọ̀ ni ìrora ẹni burúkú;

Àmọ́ ìfẹ́ Jèhófà tí kì í yẹ̀ yí ẹni tó gbẹ́kẹ̀ lé E ká.+

11 Ẹ máa yọ̀ nínú Jèhófà, kí inú yín sì máa dùn, ẹ̀yin olódodo;

Ẹ kígbe ayọ̀, gbogbo ẹ̀yin tí ọkàn yín dúró ṣinṣin.

33 Ẹ̀yin olódodo, ẹ kígbe ayọ̀, nítorí Jèhófà.+

Ó yẹ àwọn adúróṣinṣin láti máa yìn ín.

 2 Ẹ fi háàpù dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà;

Ẹ fi orin yìn ín* pẹ̀lú ohun ìkọrin olókùn tín-ín-rín mẹ́wàá.

 3 Ẹ kọ orin tuntun sí i;+

Ẹ fi ohun ìkọrin olókùn tín-ín-rín dárà, bí ẹ ti ń kígbe ayọ̀.

 4 Nítorí ọ̀rọ̀ Jèhófà dúró ṣinṣin,+

Gbogbo ohun tó bá ṣe ló ṣeé gbẹ́kẹ̀ lé.

 5 Ó nífẹ̀ẹ́ òdodo àti ìdájọ́ òdodo.+

Ìfẹ́ Jèhófà tí kì í yẹ̀ kún inú ayé.+

 6 Ọ̀rọ̀ ni Jèhófà fi dá àwọn ọ̀run,+

Nípa èémí* ẹnu rẹ̀ sì ni gbogbo ohun tó wà nínú wọn* fi wà.

 7 Ó gbá omi òkun jọ bí ìsédò;+

Ó fi omi tó ń ru gùdù sínú àwọn ilé ìṣúra.

 8 Kí gbogbo ayé bẹ̀rù Jèhófà.+

Kí gbogbo àwọn tó ń gbé ilẹ̀ tó ń méso jáde máa bẹ̀rù rẹ̀.

 9 Nítorí ó sọ̀rọ̀, ó sì rí bẹ́ẹ̀;+

Ó pàṣẹ, àṣẹ rẹ̀ sì múlẹ̀.+

10 Jèhófà ti mú kí ohun tí àwọn orílẹ̀-èdè gbèrò* já sí òfo;+

Ó ti dojú ìmọ̀ràn* àwọn èèyàn dé.+

11 Àmọ́ àwọn ìpinnu* Jèhófà yóò dúró títí láé;+

Èrò ọkàn rẹ̀ wà láti ìran dé ìran.

12 Aláyọ̀ ni orílẹ̀-èdè tí Jèhófà jẹ́ Ọlọ́run rẹ̀,+

Àwọn èèyàn tí ó ti yàn láti jẹ́ ohun ìní rẹ̀.+

13 Jèhófà bojú wolẹ̀ láti ọ̀run;

Ó ń rí gbogbo ọmọ èèyàn.+

14 Láti ibi tó ń gbé,

Ó ń wo gbogbo àwọn tó ń gbé ayé.

15 Òun ló ń mọ ọkàn gbogbo èèyàn bí ẹni mọ ìkòkò;

Ó ń gbé gbogbo iṣẹ́ wọn yẹ̀ wò.+

16 Ọ̀pọ̀ ọmọ ogun kọ́ ló ń gba ọba là;+

Agbára ńlá kò sì lè gba ẹni tó ni ín sílẹ̀.+

17 Ìgbẹ́kẹ̀lé nínú ẹṣin pé á gbani là* jẹ́ asán;+

Agbára ńlá rẹ̀ kò sọ pé kéèyàn yè bọ́.

18 Wò ó! Ojú Jèhófà ń ṣọ́ àwọn tó bẹ̀rù rẹ̀,+

Àwọn tó ń dúró de ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀,

19 Láti gbà wọ́n* sílẹ̀ lọ́wọ́ ikú,

Kí ó sì mú kí wọ́n máa wà láàyè ní àkókò ìyàn.+

20 À* ń dúró de Jèhófà.

Òun ni olùrànlọ́wọ́ wa àti apata wa.+

21 Ọkàn wa ń yọ̀ nínú rẹ̀,

Nítorí a gbẹ́kẹ̀ lé orúkọ mímọ́ rẹ̀.+

22 Jèhófà, kí ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ wà lórí wa,+

Bí a ti ń dúró dè ọ́.+

Ti Dáfídì, nígbà tó ń ṣe bí ayírí+ níwájú Ábímélékì, tí Ábímélékì fi lé e jáde, tí ó sì lọ.

א [Áléfì]

34 Èmi yóò máa yin Jèhófà ní gbogbo ìgbà;

Ìyìn rẹ̀ yóò máa wà ní ẹnu mi nígbà gbogbo.

ב [Bétì]

 2 Èmi* yóò máa fi Jèhófà yangàn;+

Àwọn oníwà pẹ̀lẹ́ yóò gbọ́, wọn yóò sì máa yọ̀.

ג [Gímélì]

 3 Ẹ bá mi gbé Jèhófà ga;+

Ẹ jẹ́ ká jọ gbé orúkọ rẹ̀ ga.

ד [Dálétì]

 4 Mo wádìí lọ́dọ̀ Jèhófà, ó sì dá mi lóhùn.+

Ó gbà mí sílẹ̀ nínú gbogbo ohun tó ń bà mí lẹ́rù.+

ה [Híì]

 5 Ojú àwọn tó gbára lé e ń dán;

Kò sí ohun tó lè kó ìtìjú bá wọn.

ז [Sáyìn]

 6 Aláìní yìí pe Jèhófà, ó sì gbọ́.

Ó gbà á nínú gbogbo wàhálà rẹ̀.+

ח [Hétì]

 7 Áńgẹ́lì Jèhófà pàgọ́ yí àwọn tó bẹ̀rù Rẹ̀ ká,+

Ó sì ń gbà wọ́n sílẹ̀.+

ט [Tétì]

 8 Ẹ tọ́ ọ wò, kí ẹ sì rí i pé ẹni rere ni Jèhófà,+

Aláyọ̀ ni ọkùnrin tí ó fi í ṣe ibi ààbò.

י [Yódì]

 9 Ẹ bẹ̀rù Jèhófà, gbogbo ẹ̀yin ẹni mímọ́ rẹ̀,

Nítorí àwọn tó bẹ̀rù rẹ̀ kò ní ṣaláìní.+

כ [Káfì]

10 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ebi máa ń pa àwọn ọmọ kìnnìún* tó lágbára,

Àmọ́ ní ti àwọn tó ń wá Jèhófà, wọn kò ní ṣaláìní ohun rere.+

ל [Lámédì]

11 Ẹ wá, ẹ̀yin ọmọ mi, ẹ fetí sí mi;

Màá kọ́ yín ní ìbẹ̀rù Jèhófà.+

מ [Mémì]

12 Ta ló fẹ́ máa gbádùn ìgbésí ayé rẹ̀ nínú yín

Tí ó sì fẹ́ ẹ̀mí gígùn, kó lè máa rí ohun rere?+

נ [Núnì]

13 Nígbà náà, ṣọ́ ahọ́n rẹ, má ṣe sọ ohun búburú,+

Má sì fi ètè rẹ ṣẹ̀tàn.+

ס [Sámékì]

14 Jáwọ́ nínú ohun búburú, kí o sì máa ṣe rere;+

Máa wá àlàáfíà, kí o sì máa lépa rẹ̀.+

ע [Áyìn]

15 Ojú Jèhófà wà lára àwọn olódodo,+

Etí rẹ̀ sì ṣí sí igbe wọn fún ìrànlọ́wọ́.+

פ [Péè]

16 Àmọ́, Jèhófà kọjú ìjà sí àwọn tó ń ṣe ohun búburú,

Láti pa wọ́n rẹ́ kúrò láyé kí wọ́n sì di ẹni ìgbàgbé.+

צ [Sádì]

17 Wọ́n ké jáde, Jèhófà sì gbọ́;+

Ó gbà wọ́n sílẹ̀ nínú gbogbo wàhálà wọn.+

ק [Kófì]

18 Jèhófà wà nítòsí àwọn tó ní ọgbẹ́ ọkàn;+

Ó ń gba àwọn tí àárẹ̀ bá ẹ̀mí wọn* là.+

ר [Réṣì]

19 Ìṣòro* olódodo máa ń pọ̀,+

Àmọ́ Jèhófà ń gbà á sílẹ̀ nínú gbogbo rẹ̀.+

ש [Ṣínì]

20 Ó ń dáàbò bo gbogbo egungun rẹ̀;

Kò sí ìkankan nínú wọn tí a ṣẹ́.+

ת [Tọ́ọ̀]

21 Àjálù ló máa pa ẹni burúkú;

A ó sì dẹ́bi fún àwọn tó kórìíra olódodo.

22 Jèhófà ń ra ẹ̀mí* àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pa dà;

Kò sí ìkankan lára àwọn tó fi í ṣe ibi ààbò tí a ó dá lẹ́bi.+

Ti Dáfídì.

35 Jèhófà, gbèjà mi níwájú àwọn tó ń ta kò mí;+

Dojú ìjà kọ àwọn tó ń bá mi jà.+

 2 Gbé asà* rẹ àti apata ńlá,+

Kí o sì dìde láti gbèjà mi.+

 3 Yọ ọ̀kọ̀ rẹ àti àáké ogun* láti dojú kọ àwọn tó ń lépa mi.+

Sọ fún mi* pé: “Èmi ni ìgbàlà rẹ.”+

 4 Kí ìtìjú bá àwọn tó ń dọdẹ ẹ̀mí mi,* kí wọ́n sì tẹ́.+

Kí àwọn tó ń gbèrò láti pa mí sá pa dà nínú ìtìjú.

 5 Kí wọ́n dà bí ìyàngbò* nínú afẹ́fẹ́;

Kí áńgẹ́lì Jèhófà lé wọn dà nù.+

 6 Kí ọ̀nà wọn ṣókùnkùn, kí ó sì máa yọ̀ bọ̀rọ́

Bí áńgẹ́lì Jèhófà ṣe ń lépa wọn.

 7 Nítorí pé wọ́n ti dẹ àwọ̀n dè mí láìnídìí;

Wọ́n ti gbẹ́ kòtò fún mi* láìnídìí.

 8 Kí àjálù dé bá a lójijì;

Kí àwọ̀n tí ó dẹ mú òun fúnra rẹ̀;

Kí ó kó sínú rẹ̀, kí ó sì pa run.+

 9 Àmọ́ èmi* yóò máa yọ̀ nínú Jèhófà;

Èmi yóò máa yọ̀ nínú àwọn iṣẹ́ ìgbàlà rẹ̀.

10 Gbogbo egungun mi á sọ pé:

“Jèhófà, ta ló dà bí rẹ?

Ò ń gba àwọn tí kò ní olùrànlọ́wọ́ sílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn tó lágbára jù wọ́n lọ,+

O sì ń gba àwọn tí kò ní olùrànlọ́wọ́ àti tálákà lọ́wọ́ àwọn tó ń jà wọ́n lólè.”+

11 Àwọn ẹlẹ́rìí èké jáde wá,+

Wọ́n ń bi mí ní àwọn ohun tí mi ò mọ̀.

12 Wọ́n ń fi ibi san rere fún mi,+

Èyí sì mú kí n* máa ṣọ̀fọ̀.

13 Àmọ́ nígbà tí wọ́n ń ṣàìsàn, mo wọ aṣọ ọ̀fọ̀,*

Mo gbààwẹ̀ láti fi pọ́n ara mi* lójú,

Nígbà tí àdúrà mi kò sì gbà,*

14 Mò ń rìn kiri, mo sì ń ṣọ̀fọ̀ bí ẹni tí ọ̀rẹ́ rẹ̀ tàbí ọmọ ìyá rẹ̀ kú;

Ìbànújẹ́ dorí mi kodò bí ẹni tó ń ṣọ̀fọ̀ ìyá rẹ̀.

15 Àmọ́ nígbà tí mo kọsẹ̀, inú wọn dùn, wọ́n sì kóra jọ;

Wọ́n kóra jọ láti pa mí ní ibi tí wọ́n lúgọ sí dè mí;

Wọ́n ya mí sí wẹ́wẹ́, wọn ò sì dákẹ́ ọ̀rọ̀ ìbàjẹ́.

16 Àwọn tí kò ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run fi mí ṣẹ̀sín,*

Wọ́n ń wa eyín wọn pọ̀ sí mi.+

17 Jèhófà, ìgbà wo lo máa wò mí dà?+

Yọ mí* nínú ogun tí wọ́n gbé tì mí,+

Gba ẹ̀mí mi tó ṣeyebíye* lọ́wọ́ àwọn ọmọ kìnnìún.*+

18 Nígbà náà, èmi yóò máa dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ nínú ìjọ ńlá;+

Èmi yóò máa yìn ọ́ láàárín ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn.

19 Má ṣe jẹ́ kí àwọn tó sọ ara wọn di ọ̀tá mi láìnídìí yọ̀ mí;

Má ṣe jẹ́ kí àwọn tó kórìíra mi láìnídìí+ wò mí tìkà-tẹ̀gbin.+

20 Nítorí wọn kì í sọ ọ̀rọ̀ àlàáfíà,

Ṣe ni wọ́n ń fẹ̀tàn hùmọ̀ ibi sí àwọn èèyàn àlàáfíà ilẹ̀ náà.+

 21 Wọ́n lanu gbàù láti fẹ̀sùn kàn mí,

Wọ́n sọ pé: “Àháà! Àháà! Ojú wa ti rí i.”

22 O ti rí èyí ná, Jèhófà. Má ṣe dákẹ́.+

Jèhófà, má jìnnà sí mi.+

23 Dìde, kí o sì wá gbèjà mi,

Jèhófà, Ọlọ́run mi, gbèjà mi nínú ẹjọ́ mi.

24 Jèhófà Ọlọ́run mi, ṣe ìdájọ́ mi nítorí òdodo rẹ;+

Má ṣe jẹ́ kí wọ́n yọ̀ mí.

25 Kí wọ́n má ṣe sọ fún ara wọn pé: “Àháà! Ọwọ́ wa ti tẹ ohun tí à ń fẹ́!”*

Kí wọ́n má ṣe sọ pé: “A ti gbé e mì.”+

26 Kí ojú ti gbogbo wọn, kí wọ́n sì tẹ́,

Àwọn tó ń yọ̀ nítorí àjálù mi.

Kí àwọn tó ń gbé ara wọn ga sí mi gbé ìtìjú àti ẹ̀tẹ́ wọ̀ bí aṣọ.

27 Àmọ́ kí àwọn tí inú wọn ń dùn sí òdodo mi kígbe ayọ̀;

Kí wọ́n máa sọ nígbà gbogbo pé:

“Kí a gbé Jèhófà ga, ẹni tí inú rẹ̀ ń dùn sí àlàáfíà ìránṣẹ́ rẹ̀.”+

 28 Nígbà náà, ahọ́n mi yóò máa ròyìn* òdodo rẹ,+

Yóò sì máa yìn ọ́ láti àárọ̀ ṣúlẹ̀.+

Sí olùdarí. Ti Dáfídì, ìránṣẹ́ Jèhófà.

36 Ẹ̀ṣẹ̀ jinlẹ̀ lọ́kàn ẹni burúkú;

Kò sí ìbẹ̀rù Ọlọ́run lójú rẹ̀.+

 2 Ó ń pọ́n ara rẹ̀ lé ju bó ṣe yẹ lọ

Débi pé kò rí àṣìṣe ara rẹ̀, kí ó sì kórìíra rẹ̀.+

 3 Ọ̀rọ̀ ìkà àti ẹ̀tàn ló wà lẹ́nu rẹ̀;

Kì í ronú bó ṣe máa ṣe rere.

 4 Ó máa ń gbèrò ibi, kódà lórí ibùsùn rẹ̀.

Ọ̀nà tí kò dáa ló forí lé;

Kì í kọ ohun búburú sílẹ̀.

 5 Jèhófà, ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ ga dé ọ̀run,+

Òtítọ́ rẹ ga títí dé àwọsánmà.

 6 Òdodo rẹ dà bí àwọn òkè ńlá;*+

Àwọn ìdájọ́ rẹ dà bí alagbalúgbú ibú omi.+

Àti èèyàn àti ẹranko ni ò ń dá sí,* Jèhófà.+

 7 Ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ mà ṣeyebíye o, Ọlọ́run!+

Abẹ́ òjìji ìyẹ́ apá rẹ ni àwọn ọmọ èèyàn fi ṣe ibi ààbò.+

 8 Wọ́n ń mu àwọn ohun tó dára jù lọ ní* ilé rẹ ní àmutẹ́rùn,+

O sì mú kí wọ́n máa mu nínú adùn rẹ tó ń ṣàn bí odò.+

 9 Ọ̀dọ̀ rẹ ni orísun ìyè wà;+

Ipasẹ̀ ìmọ́lẹ̀ rẹ ni a fi lè rí ìmọ́lẹ̀.+

10 Máa fi ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ hàn nìṣó sí àwọn tó mọ̀ ọ́,+

Àti òdodo rẹ sí àwọn tí ọkàn wọn dúró ṣinṣin.+

11 Má ṣe jẹ́ kí ẹsẹ̀ àwọn agbéraga tẹ̀ mí mọ́lẹ̀

Tàbí kí ọwọ́ àwọn ẹni burúkú lé mi dà nù.

12 Ẹ wo àwọn aṣebi níbi tí wọ́n ṣubú sí;

A ti là wọ́n mọ́lẹ̀, wọn kò sì lè dìde.+

Ti Dáfídì.

א [Áléfì]

37 Má banú jẹ́* nítorí àwọn ẹni burúkú

Tàbí kí o jowú àwọn aṣebi.+

 2 Kíákíá ni wọ́n á gbẹ dà nù bíi koríko+

Wọ́n á sì rọ bíi koríko tútù.

ב [Bétì]

 3 Gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, kí o sì máa ṣe rere;+

Máa gbé ayé,* kí o sì máa hùwà òtítọ́.+

 4 Jẹ́ kí inú rẹ máa dùn jọjọ* nínú Jèhófà,

Yóò sì fún ọ ní àwọn ohun tí ọkàn rẹ fẹ́.

ג [Gímélì]

 5 Fi ọ̀nà rẹ lé Jèhófà lọ́wọ́;*+

Gbẹ́kẹ̀ lé e, yóò sì gbé ìgbésẹ̀ nítorí rẹ.+

 6 Yóò mú kí òdodo rẹ yọ bí ọjọ́,

Àti ìwà títọ́ rẹ bí oòrùn ọ̀sán gangan.

ד [Dálétì]

 7 Dákẹ́ jẹ́ẹ́ níwájú Jèhófà+

Kí o sì dúró* dè é.

Má banú jẹ́ nítorí ẹni

Tó gbèrò ibi, tó sì mú un ṣẹ.+

ה [Híì]

 8 Fi ìbínú sílẹ̀, kí o sì pa ìrunú tì;+

Má ṣe bínú kí o wá bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe ibi.*

 9 Nítorí a ó mú àwọn ẹni ibi kúrò,+

Àmọ́ àwọn tó gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà ni yóò jogún ayé.+

ו [Wọ́ọ̀]

10 Láìpẹ́, àwọn ẹni burúkú ò ní sí mọ́;+

Wàá wo ibi tí wọ́n wà tẹ́lẹ̀,

Wọn ò ní sí níbẹ̀.+

11 Àmọ́ àwọn oníwà pẹ̀lẹ́ ni yóò jogún ayé,+

Inú wọn yóò sì máa dùn jọjọ nínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ àlàáfíà.+

ז [Sáyìn]

12 Ẹni burúkú ń dìtẹ̀ olódodo;+

Ó ń wa eyín pọ̀ sí i.

13 Àmọ́ Jèhófà yóò fi í rẹ́rìn-ín,

Nítorí Ó mọ̀ pé ọjọ́ rẹ̀ máa dé.+

ח [Hétì]

14 Àwọn ẹni burúkú fa idà wọn yọ, wọ́n sì tẹ* ọrun wọn

Láti mú àwọn tí à ń ni lára àti àwọn aláìní balẹ̀,

Láti pa àwọn tí ọ̀nà wọn tọ́.

15 Àmọ́ idà àwọn fúnra wọn yóò gún ọkàn wọn;+

A ó sì ṣẹ́ ọrun wọn.

ט [Tétì]

16 Ohun díẹ̀ tí olódodo ní

Sàn ju ọ̀pọ̀ nǹkan tí àwọn ẹni burúkú ní.+

17 A ó ṣẹ́ apá àwọn ẹni burúkú,

Àmọ́ Jèhófà yóò ti àwọn olódodo lẹ́yìn.

י [Yódì]

18 Jèhófà mọ ohun tí àwọn aláìlẹ́bi ń bá yí,*

Ogún wọn yóò sì wà títí láé.+

19 Ní àkókò àjálù, ojú kò ní tì wọ́n;

Ní àkókò ìyàn, wọ́n á ní ọ̀pọ̀ oúnjẹ.

כ [Káfì]

20 Àmọ́ àwọn ẹni burúkú yóò ṣègbé;+

Àwọn ọ̀tá Jèhófà yóò pòórá bí ibi ìjẹko tó léwé dáadáa;

Wọ́n á pòórá bí èéfín.

ל [Lámédì]

21 Ẹni burúkú ń yá nǹkan, kì í sì í san án pa dà,

Àmọ́ olódodo lawọ́,* ó sì ń fúnni ní nǹkan.+

22 Àwọn tí Ọlọ́run bù kún yóò jogún ayé,

Àmọ́ àwọn tí Ọlọ́run gégùn-ún fún yóò pa rẹ́.+

מ [Mémì]

 23 Jèhófà máa ń darí ẹsẹ̀ ẹni*+

Nígbà tí inú Rẹ̀ bá dùn sí ọ̀nà ẹni náà.+

 24 Bí onítọ̀hún bá tiẹ̀ ṣubú, kò ní balẹ̀ pátápátá,+

Nítorí pé Jèhófà dì í lọ́wọ́ mú.*+

נ [Núnì]

25 Mo ti jẹ́ ọ̀dọ́ rí, àmọ́ ní báyìí mo ti darúgbó,

Síbẹ̀, mi ò tíì rí i kí a pa olódodo tì,+

Tàbí kí àwọn ọmọ rẹ̀ máa wá oúnjẹ* kiri.+

26 Ó máa ń yáni ní nǹkan látọkàn wá,+

Ìbùkún sì ń dúró de àwọn ọmọ rẹ̀.

ס [Sámékì]

27 Yẹra fún ohun búburú, máa ṣe rere,+

Wàá sì máa gbé ayé títí láé.

28 Nítorí Jèhófà nífẹ̀ẹ́ ìdájọ́ òdodo,

Kò sì ní kọ àwọn ẹni ìdúróṣinṣin rẹ̀ sílẹ̀.+

ע [Áyìn]

Ìgbà gbogbo ni yóò máa ṣọ́ wọn;+

Àmọ́ a ó pa àtọmọdọ́mọ àwọn ẹni burúkú rẹ́.+

 29 Àwọn olódodo ni yóò jogún ayé,+

Wọn yóò sì máa gbé inú rẹ̀ títí láé.+

פ [Péè]

30 Ẹnu olódodo ń sọ ọ̀rọ̀ ọgbọ́n,*

Ahọ́n rẹ̀ sì ń sọ nípa ìdájọ́ òdodo.+

31 Òfin Ọlọ́run rẹ̀ wà ní ọkàn rẹ̀;+

Ẹsẹ̀ rẹ̀ kò ní tàsé.+

צ [Sádì]

32 Ẹni burúkú ń ṣọ́ olódodo,

Ó sì ń wá ọ̀nà láti pa á.

33 Àmọ́ Jèhófà kò ní jẹ́ kí ọwọ́ ẹni yẹn tẹ̀ ẹ́,+

Kò sì ní dá a lẹ́bi nígbà tí wọ́n bá ṣèdájọ́ rẹ̀.+

ק [Kófì]

34 Gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, kí o sì máa rìn ní ọ̀nà rẹ̀,

Yóò gbé ọ ga láti jogún ayé.

Nígbà tí a bá pa àwọn ẹni burúkú rẹ́,+ wàá rí i.+

ר [Réṣì]

35 Mo ti rí ìkà ẹ̀dá tó jẹ́ olubi

Tó ń tẹ́ rẹrẹ bí igi tó gbẹ̀rẹ̀gẹ̀jigẹ̀ ní ilẹ̀ tó dàgbà sí.+

36 Àmọ́, ó kọjá lọ lójijì, kò sì sí mọ́;+

Mo wá a kiri, mi ò sì rí i.+

ש [Ṣínì]

37 Máa fiyè sí aláìlẹ́bi,*

Kí o sì máa wo adúróṣinṣin,+

Nítorí àlàáfíà ń dúró de ẹni yẹn ní ọjọ́ ọ̀la.+

38 Àmọ́ a ó pa gbogbo àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ rẹ́,

Ìparun ló sì ń dúró de àwọn ẹni burúkú ní ọjọ́ ọ̀la.+

ת [Tọ́ọ̀]

39 Ọ̀dọ̀ Jèhófà ni ìgbàlà àwọn olódodo ti wá;+

Òun ni odi ààbò wọn ní àkókò wàhálà.+

40 Jèhófà á ràn wọ́n lọ́wọ́, á sì gbà wọ́n sílẹ̀.+

Á gbà wọ́n sílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn ẹni burúkú, á sì gbà wọ́n là,

Nítorí òun ni wọ́n fi ṣe ibi ààbò.+

Orin Dáfídì, kí ó jẹ́ ìránnilétí.*

38 Jèhófà, má ṣe bá mi wí nínú ìbínú rẹ,

Má sì tọ́ mi sọ́nà nínú ìrunú rẹ.+

 2 Nítorí àwọn ọfà rẹ ti gún mi wọnú,

Ọwọ́ rẹ sì rìn mí mọ́lẹ̀.+

 3 Gbogbo ara mi ń ṣàìsàn* nítorí ìbínú rẹ.

Kò sí àlàáfíà nínú egungun mi nítorí ẹ̀ṣẹ̀ mi.+

 4 Àwọn àṣìṣe mi rọ̀ dẹ̀dẹ̀ lórí mi;+

Bí ẹrù tó wúwo, wọ́n ti wúwo ju ohun tí mo lè gbé.

 5 Àwọn egbò mi ti kẹ̀, wọ́n sì ń rùn

Nítorí ìwà òmùgọ̀ mi.

 6 Ìdààmú àti ìrẹ̀wẹ̀sì tó lé kenkà bá mi;

Mò ń rìn kiri nínú ìbànújẹ́ láti àárọ̀ ṣúlẹ̀.

 7 Iná ń jó nínú mi lọ́hùn-ún;*

Gbogbo ara mi ń ṣàìsàn.+

 8 Ara mi ti kú tipiri, àárẹ̀ sì ti bá mi gidigidi;

Mò ń kérora* nítorí ìdààmú tó bá ọkàn mi.

 9 Jèhófà, gbogbo ìfẹ́ ọkàn mi wà níwájú rẹ,

Ẹ̀dùn ọkàn mi kò sì pa mọ́ fún ọ.

10 Ọkàn mi ń lù kì-kì, agbára mi ti tán,

Ojú mi sì ti ṣú.*+

11 Àwọn ọ̀rẹ́ mi àti àwọn ẹlẹgbẹ́ mi yẹra fún mi nítorí ìyọnu tó dé bá mi,

Àwọn ojúlùmọ̀ tó sún mọ́ mi sì ta kété sí mi.

12 Àwọn tó ń wá ẹ̀mí* mi dẹ pańpẹ́ sílẹ̀;

Àwọn tó fẹ́ ṣe mí léṣe ń sọ nípa ìparun;+

Ẹ̀tàn ni wọ́n ń sọ lẹ́nu wúyẹ́wúyẹ́ láti àárọ̀ ṣúlẹ̀.

13 Àmọ́, màá ṣe bí adití, mi ò ní fetí sí wọn;+

Màá ṣe bí ẹni tí kò lè sọ̀rọ̀, mi ò ní la ẹnu mi.+

14 Mo dà bí ẹni tí kò gbọ́ràn,

Tí kò ní nǹkan kan tó máa sọ láti gbèjà ara rẹ̀.

15 Nítorí ìwọ Jèhófà ni mo dúró dè,+

O sì dá mi lóhùn, Jèhófà Ọlọ́run mi.+

16 Torí mo sọ pé: “Kí wọ́n má yọ̀ mí,

Kí wọ́n má sì gbé ara wọn ga sí mi tí ẹsẹ̀ mi bá yẹ̀.”

17 Nítorí mo ti fẹ́ ṣubú lulẹ̀,

Ara sì ń ro mí nígbà gbogbo.+

18 Mo jẹ́wọ́ àṣìṣe mi;+

Ẹ̀ṣẹ̀ mi dààmú mi.+

19 Àmọ́ àwọn ọ̀tá mi lókun,* wọ́n sì lágbára,*

Àwọn tó kórìíra mi láìnídìí ti pọ̀ gan-an.

20 Wọ́n ń fi ibi san ire fún mi;

Wọ́n ń ta kò mí nítorí mò ń lépa ohun rere.

21 Má fi mí sílẹ̀, Jèhófà.

Má jìnnà sí mi,+ Ọlọ́run mi.

 22 Tètè wá ràn mí lọ́wọ́,

Jèhófà, ìgbàlà mi.+

Sí olùdarí; ti Jédútúnì.*+ Orin Dáfídì.

39 Mo sọ pé: “Màá ṣọ́ ẹsẹ̀ mi

Kí n má bàa fi ahọ́n mi dẹ́ṣẹ̀.+

Màá fi ìbonu bo ẹnu mi+

Ní gbogbo ìgbà tí ẹni burúkú bá wà níwájú mi.”

 2 Mi ò lè sọ̀rọ̀, ṣe ni mo dákẹ́;+

Mi ò sọ nǹkan kan, kódà nípa ohun rere,

Síbẹ̀, ìrora mi le kọjá sísọ.*

 3 Ọkàn mi rọra ń jó* nínú mi bí iná.

Bí mo ṣe ń ronú* ni iná náà ń jó.

Ahọ́n mi wá sọ pé:

 4 “Jèhófà, jẹ́ kí n mọ ohun tó máa gbẹ̀yìn mi

Àti bí ọjọ́ ayé mi ṣe máa gùn tó,+

Kí n lè mọ bí ẹ̀mí mi ṣe kúrú tó.*

 5 Lóòótọ́, o ti mú kí ọjọ́ ayé mi kéré;*+

Gbogbo ọjọ́ ayé mi kò sì jẹ́ nǹkan kan lójú rẹ.+

Ní ti ọmọ èèyàn, bó tilẹ̀ dà bíi pé kò sí nínú ewu, bí èémí lásán ló rí.+ (Sélà)

 6 Dájúdájú, bí òjìji ni ọmọ èèyàn ń rìn kiri.

Ó ń sáré kiri* lórí òfo.

Ó ń kó ọrọ̀ jọ pelemọ láìmọ ẹni tó máa gbádùn rẹ̀.+

 7 Kí wá ni kí n máa retí, Jèhófà?

Ìwọ nìkan ni ìrètí mi.

 8 Yọ mí nínú gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ mi.+

Má ṣe jẹ́ kí àwọn òmùgọ̀ sọ mí di ẹni ẹ̀gàn.

 9 Mi ò lè sọ̀rọ̀;

Mi ò lè la ẹnu mi,+

Nítorí iṣẹ́ ọwọ́ rẹ ni.+

10 Mú ìyọnu rẹ kúrò lórí mi.

Àárẹ̀ mú mi nítorí ọwọ́ rẹ ti gbá mi.

11 O fi ìyà tọ́ èèyàn sọ́nà nítorí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀;+

O run nǹkan tó kà sí iyebíye bí ìgbà tí òólá* bá jẹ nǹkan.

Dájúdájú, èémí lásán ni ọmọ èèyàn.+ (Sélà)

12 Gbọ́ àdúrà mi, Jèhófà,

Fetí sí igbe mi fún ìrànlọ́wọ́.+

Má ṣe gbójú fo omijé mi.

Nítorí àjèjì lásán ni mo jẹ́ sí ọ,+

Arìnrìn-àjò tó ń kọjá lọ* ni mí, bíi gbogbo àwọn baba ńlá mi.+

13 Má ṣe wò mí nínú ìbínú rẹ, kí n lè túra ká

Kí n tó kọjá lọ tí mi ò sì ní sí mọ́.”

Sí olùdarí. Ti Dáfídì. Orin.

40 Taratara ni mo fi* dúró de Jèhófà,

Ó fetí sí mi,* ó sì gbọ́ igbe mi fún ìrànlọ́wọ́.+

 2 Ó gbé mi jáde látinú kòtò tó ní ìró omi púpọ̀,

Láti inú ẹrẹ̀.

Ó sì fi ẹsẹ̀ mi lé orí àpáta;

Ó fi ẹsẹ̀ mi múlẹ̀ ṣinṣin.

 3 Ó wá fi orin tuntun sí mi lẹ́nu,+

Ìyìn sí Ọlọ́run wa.

Ọ̀pọ̀ èèyàn á rí nǹkan yìí, ẹ̀rù Ọlọ́run á bà wọ́n,

Wọ́n á sì gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà.

 4 Aláyọ̀ ni ọkùnrin tó gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà,

Tí kò sì yíjú sí àwọn aláfojúdi tàbí àwọn ẹlẹ́tàn.*

 5 Wo bí àwọn ohun tí o ṣe ti pọ̀ tó,

Jèhófà Ọlọ́run mi,

Àwọn iṣẹ́ àgbàyanu rẹ àti èrò rẹ sí wa.+

Kò sí ẹni tí a lè fi ọ́ wé;+

Tí mo bá ní kí n máa wí, kí n sì máa sọ nípa wọn,

Wọ́n pọ̀ ju ohun tí mo lè ròyìn!+

 6 Ẹbọ àti ọrẹ kọ́ ni ohun tó wù ọ́,*+

Àmọ́ o la etí mi sílẹ̀ kí n lè gbọ́.+

O kò béèrè ẹbọ sísun àti ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀.+

 7 Lẹ́yìn náà, mo sọ pé: “Wò ó, mo ti dé.

A ti kọ ọ́ nípa mi sínú àkájọ ìwé.+

 8 Láti ṣe ìfẹ́ rẹ, Ọlọ́run mi, ni inú mi dùn sí,*+

Òfin rẹ sì wà nínú mi lọ́hùn-ún.+

 9 Mo kéde ìhìn rere òdodo nínú ìjọ ńlá.+

Wò ó! Mi ò pa ẹnu mi mọ́,+

Bí ìwọ náà ṣe mọ̀ dáadáa, Jèhófà.

10 Mi ò bo òdodo rẹ mọ́lẹ̀ nínú ọkàn mi.

Mo kéde ìṣòtítọ́ rẹ àti ìgbàlà rẹ.

Mi ò fi ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ àti òtítọ́ rẹ pa mọ́ nínú ìjọ ńlá.”+

11 Jèhófà, má ṣe fawọ́ àánú rẹ sẹ́yìn lórí mi.

Kí ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ àti òtítọ́ rẹ máa dáàbò bò mí nígbà gbogbo.+

12 Àwọn àjálù tó yí mi ká kò ṣeé kà.+

Àwọn àṣìṣe mi pọ̀ débi pé mi ò tiẹ̀ mọ ibi tí mo forí lé;+

Wọ́n pọ̀ ju irun orí mi lọ,

Ìrẹ̀wẹ̀sì sì ti bá ọkàn mi.

13 Jọ̀ọ́ Jèhófà, jẹ́ kó wù ọ́ láti gbà mí sílẹ̀.+

Jèhófà, tètè wá ràn mí lọ́wọ́.+

14 Kí ìtìjú àti ẹ̀tẹ́ bá

Gbogbo àwọn tó fẹ́ gba ẹ̀mí mi.*

Kí àwọn tí inú wọn ń dùn sí àjálù tó bá mi

Sá pa dà nínú ẹ̀tẹ́.

15 Ní ti àwọn tó ń sọ nípa mi pé: “Àháà! Àháà!”

Kí jìnnìjìnnì bò wọ́n nítorí ìtìjú tó dé bá wọn.

16 Àmọ́ kí àwọn tó ń wá ọ+

Máa yọ̀, kí inú wọn sì máa dùn nítorí rẹ.+

Kí àwọn tó nífẹ̀ẹ́ àwọn iṣẹ́ ìgbàlà rẹ máa sọ nígbà gbogbo pé:

“Ẹ gbé Jèhófà ga.”+

17 Àmọ́ aláìní ni mí, mi ò sì ní olùrànlọ́wọ́;

Kí Jèhófà fiyè sí mi.

Ìwọ ni olùrànlọ́wọ́ mi àti olùgbàlà mi;+

Ọlọ́run mi, má ṣe jẹ́ kó pẹ́.+

Sí olùdarí. Orin Dáfídì.

41 Aláyọ̀ ni ẹni tó bá ń ro ti àwọn aláìní;+

Jèhófà yóò gbà á sílẹ̀ ní ọjọ́ àjálù.

 2 Jèhófà yóò dáàbò bò ó, yóò sì pa á mọ́.

A ó pè é ní aláyọ̀ ní ayé;+

O kò sì ní jẹ́ kí èrò* àwọn ọ̀tá rẹ̀ ṣẹ lé e lórí.+

 3 Jèhófà yóò fún un lókun lórí ibùsùn àìsàn rẹ̀;+

Ìwọ yóò pààrọ̀ ibùsùn rẹ̀ nígbà tó ń ṣàìsàn.

 4 Mo sọ pé: “Jèhófà, ṣojú rere sí mi.+

Wò mí* sàn,+ torí mo ti ṣẹ̀ sí ọ.”+

 5 Àmọ́ àwọn ọ̀tá mi ń sọ ọ̀rọ̀ burúkú nípa mi pé:

“Ìgbà wo ló máa kú, tí orúkọ rẹ̀ á sì pa rẹ́?”

 6 Tí ọ̀kan nínú wọn bá wá rí mi, irọ́ tó wà lọ́kàn rẹ̀ lá máa pa.

Ọ̀rọ̀ tó ń dunni lá máa kó jọ;

Lẹ́yìn náà, á jáde lọ, á sì máa sọ ọ́ kiri.

 7 Gbogbo àwọn tó kórìíra mi ń bára wọn sọ̀rọ̀ wúyẹ́wúyẹ́;

Wọ́n ń gbèrò ibi sí mi pé:

 8 “Ohun tó ń bani lẹ́rù ti dé bá a;

Ní báyìí tó ti ṣubú lulẹ̀, kò ní dìde mọ́.”+

 9 Kódà, ẹni tó wà ní àlàáfíà pẹ̀lú mi, tí mo fọkàn tán,+

Ẹni tí a jọ ń jẹun, ti jìn mí lẹ́sẹ̀.*+

10 Àmọ́, Jèhófà, ṣojú rere sí mi, kí o sì gbé mi dìde,

Kí n lè san án pa dà fún wọn.

11 Ohun tí màá fi mọ̀ pé inú rẹ dùn sí mi nìyí:

Kí àwọn ọ̀tá mi má lè kígbe ìṣẹ́gun lé mi lórí.+

12 Ní tèmi, o ti dì mí mú nítorí ìwà títọ́ mi;+

Wàá fi mí sí iwájú rẹ títí láé.+

13 Ìyìn ni fún Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì

Títí láé àti láéláé.*+

Àmín àti Àmín.

ÌWÉ KEJÌ

(Sáàmù 42-72)

Sí olùdarí. Másíkílì* àwọn ọmọ Kórà.+

42 Bí ọkàn àgbọ̀nrín ṣe máa ń fà sí odò,

Bẹ́ẹ̀ ni ọkàn mi ṣe ń fà sí ọ, ìwọ Ọlọ́run mi.

 2 Mò* ń wá Ọlọ́run, Ọlọ́run alààyè, bí ẹni tí òùngbẹ ń gbẹ ṣe ń wá omi.+

Ìgbà wo ni kí n wá, kí n sì fara hàn níwájú Ọlọ́run?+

 3 Omijé mi ni oúnjẹ mi lọ́sàn-án àti lóru;

Láti àárọ̀ ṣúlẹ̀, wọ́n ń fi mí ṣẹ̀sín, wọ́n ń sọ pé: “Ọlọ́run rẹ dà?”+

 4 Mo rántí àwọn nǹkan yìí, mo sì tú ọkàn* mi jáde,

Torí pé, nígbà kan, mo ti bá ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn rìn;

Mo máa ń rìn tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀* níwájú wọn lọ sí ilé Ọlọ́run,

Pẹ̀lú igbe ayọ̀ àti ti ọpẹ́,

Ti ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ èèyàn tó ń ṣàjọyọ̀.+

 5 Kí nìdí tí ìrẹ̀wẹ̀sì fi bá ẹ̀mí* mi?+

Kí nìdí tí ìdààmú fi bá ọkàn mi?

Dúró de Ọlọ́run,+

Nítorí mo ṣì máa yìn ín torí òun ni Olùgbàlà mi Atóbilọ́lá.+

 6 Ọlọ́run mi, ìrẹ̀wẹ̀sì ti bá ẹ̀mí* mi.+

Ìdí nìyẹn tí mo fi rántí rẹ,+

Láti ilẹ̀ Jọ́dánì àti àwọn téńté orí Hámónì,

Láti Òkè Mísárì.*

 7 Ibú omi ń pe ibú omi

Nígbà tí àwọn omi rẹ tó ń dà ṣọ̀ọ̀rọ̀ ń dún.

Gbogbo omi rẹ tó ń ru gùdù ti bò mí mọ́lẹ̀.+

 8 Ní ọ̀sán, Jèhófà yóò fi ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ hàn sí mi,

Ní òru, orin rẹ̀ yóò wà lẹ́nu mi, ìyẹn àdúrà sí Ọlọ́run tó fún mi ní ẹ̀mí.+

 9 Màá sọ fún Ọlọ́run, àpáta mi pé:

“Kí nìdí tí o fi gbàgbé mi?+

Kí nìdí tí mo fi ń rìn kiri nínú ìbànújẹ́ nítorí pé ọ̀tá mi ń ni mí lára?”+

10 Àwọn ọ̀tá mi ń fi mí ṣẹ̀sín nítorí ìkórìíra tó lágbára tí wọ́n ní sí mi;*

Láti àárọ̀ ṣúlẹ̀, wọ́n ń fi mí ṣẹ̀sín, wọ́n ń sọ pé: “Ọlọ́run rẹ dà?”+

11 Kí nìdí tí ìrẹ̀wẹ̀sì fi bá ẹ̀mí* mi?

Kí nìdí tí ìdààmú fi bá ọkàn mi?

Dúró de Ọlọ́run,+

Nítorí mo ṣì máa yìn ín torí òun ni Olùgbàlà mi Atóbilọ́lá àti Ọlọ́run mi.+

43 Ṣe ìdájọ́ mi, Ọlọ́run,+

Gbèjà mi+ níwájú orílẹ̀-èdè aláìṣòótọ́.

Gbà mí lọ́wọ́ ẹlẹ́tàn àti aláìṣòdodo.

 2 Nítorí pé ìwọ ni Ọlọ́run mi, odi ààbò mi.+

Kí nìdí tí o fi ta mí nù?

Kí nìdí tí mo fi ń rìn kiri nínú ìbànújẹ́ nítorí pé ọ̀tá mi ń ni mí lára?+

 3 Rán ìmọ́lẹ̀ rẹ àti òtítọ́ rẹ jáde.+

Kí wọ́n máa darí mi;+

Kí wọ́n ṣamọ̀nà mi sí òkè mímọ́ rẹ àti sí àgọ́ ìjọsìn rẹ títóbi.+

 4 Nígbà náà, màá wá síbi pẹpẹ Ọlọ́run,+

Sọ́dọ̀ Ọlọ́run, tí ó jẹ́ ayọ̀ ńlá mi.

Màá sì fi háàpù yìn ọ́,+ ìwọ Ọlọ́run, Ọlọ́run mi.

 5 Kí nìdí tí ìrẹ̀wẹ̀sì fi bá ẹ̀mí* mi?

Kí nìdí tí ìdààmú fi bá ọkàn mi?

Dúró de Ọlọ́run,+

Nítorí mo ṣì máa yìn ín torí òun ni Olùgbàlà mi Atóbilọ́lá àti Ọlọ́run mi.+

Sí olùdarí. Ti àwọn ọmọ Kórà.+ Másíkílì.*

44 Ọlọ́run, a ti fi etí wa gbọ́,

Àwọn baba ńlá wa ti ròyìn fún wa,+

Àwọn ohun tí o ṣe nígbà ayé wọn,

Ní àwọn ọjọ́ tó ti pẹ́.

 2 Ọwọ́ rẹ ni o fi lé àwọn orílẹ̀-èdè jáde,+

O sì mú kí àwọn baba ńlá wa máa gbé níbẹ̀.+

O fọ́ àwọn orílẹ̀-èdè, o sì lé wọn jáde.+

 3 Kì í ṣe idà wọn ni wọ́n fi gba ilẹ̀ náà,+

Kì í sì í ṣe apá wọn ló mú kí wọ́n ṣẹ́gun.+

Kàkà bẹ́ẹ̀, ọwọ́ ọ̀tún rẹ àti apá rẹ+ àti ìmọ́lẹ̀ ojú rẹ ló ṣe é,

Nítorí pé inú rẹ dùn sí wọn.+

 4 Ìwọ Ọlọ́run ni Ọba mi;+

Pàṣẹ ìṣẹ́gun pípé fún Jékọ́bù.*

 5 Agbára rẹ la ó fi lé àwọn ọ̀tá wa pa dà;+

Orúkọ rẹ la ó fi tẹ àwọn tó dìde sí wa rẹ́.+

 6 Torí mi ò gbẹ́kẹ̀ lé ọfà* mi,

Idà mi ò sì lè gbà mí là.+

 7 Ìwọ lo gbà wá lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá wa,+

Ìwọ lo sì kó ìtìjú bá àwọn tó kórìíra wa.

 8 A ó máa yin Ọlọ́run láti àárọ̀ ṣúlẹ̀,

A ó sì máa fi ọpẹ́ fún orúkọ rẹ títí láé. (Sélà)

 9 Àmọ́ ní báyìí, o ti ta wá nù, o ti kó ìtìjú bá wa,

O ò sì bá àwọn ọmọ ogun wa jáde.

10 Ò ń mú kí a sá pa dà níwájú àwọn ọ̀tá wa;+

Àwọn tó kórìíra wa ń kó ohun tí wọ́n fẹ́.

11 O fi wá lé wọn lọ́wọ́ kí wọ́n lè pa wá jẹ bí àgùntàn;

O ti tú wa ká sáàárín àwọn orílẹ̀-èdè.+

12 O ta àwọn èèyàn rẹ lọ́pọ̀;+

O ò jẹ èrè kankan lórí wọn.*

13 O sọ wá di ẹni ẹ̀gàn lójú àwọn aládùúgbò wa,

Ẹni ẹ̀sín àti ẹni yẹ̀yẹ́ lójú àwọn tó yí wa ká.

14 O sọ wá di ẹni ẹ̀gàn* láàárín àwọn orílẹ̀-èdè,+

Ẹni tí àwọn èèyàn ń rí, tí wọ́n ń mi orí.

15 Ẹ̀tẹ́ bá mi láti àárọ̀ ṣúlẹ̀,

Ìtìjú mi sì ti bò mí mọ́lẹ̀,

16 Torí ẹ̀sín tí wọ́n ń fi mí ṣe àti èébú wọn,

Nítorí pé ọ̀tá wa ń gbẹ̀san lára wa.

17 Gbogbo èyí ti ṣẹlẹ̀ sí wa, síbẹ̀ a kò gbàgbé rẹ,

A kò sì da májẹ̀mú rẹ.+

18 Ọkàn wa kò kúrò lọ́dọ̀ rẹ;

Ẹsẹ̀ wa kò yà kúrò ní ọ̀nà rẹ.

19 Àmọ́ o ti tẹ̀ wá rẹ́ níbi tí àwọn ajáko* ń gbé;

O ti fi òkùnkùn biribiri bò wá mọ́lẹ̀.

20 Ká ní a ti gbàgbé orúkọ Ọlọ́run wa

Tàbí tí a tẹ́wọ́ àdúrà sí ọlọ́run àjèjì,

21 Ṣé Ọlọ́run kò ní mọ̀ ni?

Ó mọ àwọn àṣírí tó wà nínú ọkàn.+

22 Torí rẹ ni wọ́n ṣe ń pa wá láti àárọ̀ ṣúlẹ̀;

Wọ́n ti kà wá sí àgùntàn tó wà fún pípa.+

23 Dìde. Kí ló dé tí o ṣì fi ń sùn, Jèhófà?+

Jí! Má ṣe ta wá nù títí láé.+

24 Kí ló dé tí o fi fojú rẹ pa mọ́?

Kí ló dé tí o fi gbàgbé ìyà tó ń jẹ wá àti ìnira tó bá wa?

25 Nítorí wọ́n ti bá wa* kanlẹ̀;

Wọ́n sì ti tẹ̀ wá mọ́lẹ̀.+

26 Dìde nítorí ìwọ ni olùrànlọ́wọ́ wa!+

Gbà wá sílẹ̀* nítorí ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀.+

Sí olùdarí; kí a yí i sí “Òdòdó Lílì.” Ti àwọn ọmọ Kórà.+ Másíkílì.* Orin ìfẹ́.

45 Ohun rere kan ń gbé mi lọ́kàn.

Mo sọ pé: “Orin mi dá lórí* ọba kan.”+

Kí ahọ́n mi jẹ́ kálàmù*+ ọ̀jáfáfá adàwékọ.*+

 2 Ìwọ lo rẹwà jù lọ nínú àwọn ọmọ èèyàn.

Ọ̀rọ̀ rere ń jáde lẹ́nu rẹ.+

Ìdí nìyẹn tí Ọlọ́run fi bù kún ọ títí láé.+

 3 Sán idà rẹ+ mọ́ ìdí rẹ, ìwọ alágbára ńlá,+

Nínú iyì rẹ àti ọlá ńlá rẹ.+

 4 Nínú ọlá ńlá rẹ, kí o ṣẹ́gun;*+

Máa gẹṣin lọ nítorí òtítọ́ àti ìrẹ̀lẹ̀ àti òdodo,+

Ọwọ́ ọ̀tún rẹ yóò sì ṣe* àwọn ohun àgbàyanu.

 5 Àwọn ọfà rẹ mú, wọ́n ń mú kí àwọn èèyàn ṣubú níwájú rẹ;+

Wọ́n ń gún ọkàn àwọn ọ̀tá ọba.+

 6 Ọlọ́run ni ìtẹ́ rẹ títí láé àti láéláé;+

Ọ̀pá àṣẹ ìjọba rẹ jẹ́ ọ̀pá àṣẹ ìdúróṣinṣin.*+

 7 O nífẹ̀ẹ́ òdodo,+ o sì kórìíra ìwà burúkú.+

Ìdí nìyẹn tí Ọlọ́run, àní Ọlọ́run rẹ, fi fòróró ayọ̀+ yàn ọ́+ ju àwọn ojúgbà rẹ.

 8 Òjíá àti álóè àti kaṣíà ń já fíkán lára gbogbo aṣọ rẹ;

Ìró àwọn ohun ìkọrin olókùn tín-ín-rín látinú ààfin títóbi lọ́lá tí a fi eyín erin ṣe lọ́ṣọ̀ọ́ ń mú inú rẹ dùn.

 9 Àwọn ọmọbìnrin àwọn ọba wà lára àwọn obìnrin ọlọ́lá rẹ.

Ayaba* dúró ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ, a fi wúrà Ófírì+ ṣe é lọ́ṣọ̀ọ́.

10 Gbọ́, ìwọ ọmọbìnrin, fiyè sí i, kí o sì fetí sílẹ̀;

Gbàgbé àwọn èèyàn rẹ àti ilé bàbá rẹ.

11 Ọkàn ọba yóò máa fà sí ọ nítorí ẹwà rẹ,

Torí òun ni olúwa rẹ,

Nítorí náà, tẹrí ba fún un.

12 Ọmọbìnrin Tírè máa mú ẹ̀bùn wá;

Àwọn tó lọ́rọ̀ jù lọ máa wá ojú rere rẹ.*

13 Nínú ààfin,* ọmọbìnrin ọba gbé ògo wọ̀ bí aṣọ;

A fi wúrà ṣe aṣọ rẹ̀ lọ́ṣọ̀ọ́.*

14 A ó mú un wá sọ́dọ̀ ọba nínú aṣọ tí a hun dáadáa.*

A ó mú àwọn wúńdíá ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ tó ń tẹ̀ lé e wọlé síwájú rẹ.

15 A ó mú wọn wá pẹ̀lú ayọ̀ àti ìdùnnú,

Wọ́n á sì wọ ààfin ọba.

16 Àwọn ọmọkùnrin rẹ yóò gba ipò àwọn baba ńlá rẹ.

Wàá yàn wọ́n ṣe olórí ní gbogbo ayé.+

17 Màá jẹ́ kí àwọn èèyàn mọ orúkọ rẹ jálẹ̀ gbogbo ìran tó ń bọ̀.+

Ìdí nìyẹn tí àwọn èèyàn á fi máa yìn ọ́ títí láé àti láéláé.

Sí olùdarí. Ti àwọn ọmọ Kórà.+ Lọ́nà ti Álámótì.* Orin.

46 Ọlọ́run ni ibi ààbò wa àti okun wa,+

Ìrànlọ́wọ́ tó wà lárọ̀ọ́wọ́tó ní àkókò wàhálà.+

 2 Ìdí nìyẹn tí a kò fi ní bẹ̀rù, bí ayé tilẹ̀ ń mì tìtì,

Bí àwọn òkè tilẹ̀ ń ṣubú sínú ibú òkun,+

 3 Bí omi rẹ̀ tilẹ̀ ń pariwo, tó sì ń ru sókè,*+

Bí àwọn òkè tilẹ̀ ń mì jìgìjìgì nítorí ìrugùdù rẹ̀. (Sélà)

 4 Odò kan wà tí ṣíṣàn rẹ̀ ń mú kí ìlú Ọlọ́run máa yọ̀,+

Àgọ́ ìjọsìn mímọ́ títóbi ti Ẹni Gíga Jù Lọ.

 5 Ọlọ́run wà nínú ìlú náà;+ kò ṣeé bì ṣubú.

Ọlọ́run á ràn án lọ́wọ́ tí ilẹ̀ bá mọ́.+

 6 Àwọn orílẹ̀-èdè wà nínú rúkèrúdò, àwọn ìjọba ń ṣubú;

Ó gbé ohùn rẹ̀ sókè, ayé sì yọ́.+

 7 Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun wà pẹ̀lú wa;+

Ọlọ́run Jékọ́bù ni ibi ààbò wa.* (Sélà)

 8 Ẹ wá wo àwọn iṣẹ́ Jèhófà,

Bí ó ṣe gbé àwọn ohun àgbàyanu ṣe ní ayé.

 9 Ó ń fòpin sí ogun kárí ayé.+

Ó ṣẹ́ ọrun, ó sì kán ọ̀kọ̀ sí wẹ́wẹ́;

Ó sun àwọn kẹ̀kẹ́ ogun* nínú iná.

10 “Ẹ túúbá, kí ẹ sì mọ̀ pé èmi ni Ọlọ́run.

A ó gbé mi ga láàárín àwọn orílẹ̀-èdè;+

A ó gbé mi ga ní ayé.”+

11 Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun wà pẹ̀lú wa;+

Ọlọ́run Jékọ́bù jẹ́ ibi ààbò fún wa.+ (Sélà)

Sí olùdarí. Ti àwọn ọmọ Kórà.+ Orin.

47 Gbogbo ẹ̀yin èèyàn, ẹ pàtẹ́wọ́.

Ẹ fi ayọ̀ kígbe ìṣẹ́gun sí Ọlọ́run.

 2 Nítorí Jèhófà Ẹni Gíga Jù Lọ yẹ lẹ́ni tí à ń bẹ̀rù;+

Òun ni Ọba ńlá lórí gbogbo ayé.+

 3 Ó tẹ àwọn èèyàn lórí ba lábẹ́ wa;

Ó fi àwọn orílẹ̀-èdè sábẹ́ ẹsẹ̀ wa.+

 4 Ó yan ogún wa fún wa,+

Ògo Jékọ́bù, ẹni tó nífẹ̀ẹ́.+ (Sélà)

 5 Ọlọ́run ti gòkè nígbà tí àwọn èèyàn ń kígbe ayọ̀,

Jèhófà ti gòkè nígbà tí àwọn èèyàn ń fun ìwo.*

 6 Ẹ kọ orin ìyìn* sí Ọlọ́run, ẹ kọ orin ìyìn.

Ẹ kọ orin ìyìn sí Ọba wa, ẹ kọ orin ìyìn.

 7 Nítorí Ọlọ́run ni Ọba gbogbo ayé;+

Ẹ kọ orin ìyìn, kí ẹ sì fi ìjìnlẹ̀ òye hàn.

 8 Ọlọ́run ti di Ọba lórí àwọn orílẹ̀-èdè.+

Ọlọ́run jókòó lórí ìtẹ́ mímọ́ rẹ̀.

 9 Àwọn olórí àwọn èèyàn ti kóra jọ

Pẹ̀lú àwọn èèyàn Ọlọ́run Ábúráhámù.

Nítorí àwọn alákòóso* ayé jẹ́ ti Ọlọ́run.

A ti gbé e ga sókè.+

Orin. Orin àwọn ọmọ Kórà.+

48 Jèhófà tóbi, òun sì ni ìyìn yẹ jù lọ

Ní ìlú Ọlọ́run wa, ní òkè mímọ́ rẹ̀.

 2 Gíga rẹ̀ rẹwà, ayọ̀ gbogbo ayé,+

Òkè Síónì tó jìnnà réré ní àríwá,

Ìlú Ọba Títóbi Lọ́lá.+

 3 Nínú àwọn ilé gogoro rẹ̀ tó láàbò,

Ọlọ́run ti jẹ́ kí a mọ̀ pé òun ni ibi ààbò.*+

 4 Wò ó! àwọn ọba ti kóra jọ;*

Wọ́n jọ tẹ̀ síwájú.

 5 Nígbà tí wọ́n rí i, ẹnu yà wọ́n.

Jìnnìjìnnì bá wọn, wọ́n sì sá kìjokìjo.

 6 Ìbẹ̀rù mú wọn níbẹ̀,

Ìrora bíi ti obìnrin tó ń rọbí.

 7 O fi ẹ̀fúùfù ìlà oòrùn fọ́ àwọn ọkọ̀ òkun Táṣíṣì.

 8 A ti wá fi ojú wa rí ohun tí a ti gbọ́

Ní ìlú Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun, ní ìlú Ọlọ́run wa.

Ọlọ́run yóò fìdí rẹ̀ múlẹ̀ ṣinṣin títí láé.+ (Sélà)

 9 A ronú lórí ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀, Ọlọ́run,+

Nínú tẹ́ńpìlì rẹ.

10 Bí orúkọ rẹ ṣe lọ, Ọlọ́run, bẹ́ẹ̀ ni ìyìn rẹ

Ṣe lọ títí dé ìkángun ayé.+

Òdodo kún ọwọ́ ọ̀tún rẹ.+

11 Kí inú Òkè Síónì+ máa dùn,

Kí àwọn ìlú* Júdà sì máa yọ̀, nítorí àwọn ìdájọ́ rẹ.+

12 Ẹ rìn yí ká Síónì; ẹ lọ káàkiri inú rẹ̀;

Ẹ ka àwọn ilé gogoro rẹ̀.+

13 Ẹ kíyè sí àwọn òkìtì tó wà lẹ́yìn ògiri rẹ̀.*+

Ẹ ṣàyẹ̀wò àwọn ilé gogoro rẹ̀ tó láàbò,

Kí ẹ lè ròyìn rẹ̀ fún ìran ọjọ́ iwájú.

14 Nítorí Ọlọ́run yìí ni Ọlọ́run wa+ títí láé àti láéláé.

Yóò máa ṣamọ̀nà wa títí láé.*+

Sí olùdarí. Ti àwọn ọmọ Kórà.+ Orin.

49 Ẹ gbọ́, gbogbo ẹ̀yin èèyàn.

Ẹ fiyè sí i, gbogbo ẹ̀yin tó ń gbé ayé,*

 2 Ẹni kékeré àti ẹni ńlá,*

Àti olówó àti tálákà.

 3 Ẹnu mi yóò sọ̀rọ̀ ọgbọ́n,

Àṣàrò ọkàn mi+ yóò sì fi òye hàn.

 4 Màá fiyè sí òwe;

Màá fi háàpù pa àlọ́ mi.

 5 Kí nìdí tí màá fi máa bẹ̀rù nígbà wàhálà,+

Nígbà tí ìwà ibi* àwọn tó fẹ́ lé mi kúrò yí mi ká?

 6 Àwọn tí wọ́n gbẹ́kẹ̀ lé ọrọ̀ wọn,+

Tí wọ́n sì ń fi ọrọ̀ rẹpẹtẹ wọn fọ́nnu,+

 7 Kò sí ìkankan nínú wọn tó lè ra arákùnrin kan pa dà

Tàbí tí ó lè fún Ọlọ́run ní ìràpadà nítorí rẹ̀,+

 8 (Iye owó ìràpadà ẹ̀mí* wọn ṣe iyebíye

Débi pé ó kọjá ohun tí ọwọ́ wọn lè tẹ̀);

 9 Tí á fi wà láàyè títí láé, tí kò sì ní rí kòtò.*+

10 Gbogbo èèyàn ló mọ̀ pé àwọn ọlọ́gbọ́n pàápàá ń kú;

Àwọn òmùgọ̀ àti àwọn aláìnírònú ń ṣègbé pa pọ̀,+

Wọ́n á sì fi ọrọ̀ wọn sílẹ̀ fún àwọn ẹlòmíì.+

11 Ohun tó ń wù wọ́n lọ́kàn ni pé kí ilé wọn wà títí láé,

Kí àgọ́ wọn wà láti ìran dé ìran.

Wọ́n ti fi orúkọ wọn pe àwọn ilẹ̀ wọn.

12 Àmọ́ bí a tilẹ̀ dá èèyàn lọ́lá, kò lè máa wà nìṣó;+

Kò sàn ju àwọn ẹranko tó ń ṣègbé.+

13 Bí ọ̀nà àwọn òmùgọ̀ ṣe rí nìyí+

Àti ti àwọn tó ń tẹ̀ lé wọn, tí inú wọn ń dùn sí ọ̀rọ̀ asán tí wọ́n ń sọ. (Sélà)

14 A ti yàn wọ́n bí àgùntàn láti lọ sí Isà Òkú.*

Ikú yóò ṣe olùṣọ́ àgùntàn wọn;

Àwọn adúróṣinṣin yóò ṣàkóso wọn+ ní òwúrọ̀.

Wọ́n á pa rẹ́, tí a ò ní rí ipa wọn mọ́;+

Isà Òkú*+ ló máa di ilé wọn dípò ààfin.+

15 Àmọ́, Ọlọ́run máa rà mí* pa dà kúrò lọ́wọ́ agbára* Isà Òkú,*+

Nítorí ó máa dì mí mú. (Sélà)

16 Má bẹ̀rù nítorí pé ẹnì kan di ọlọ́rọ̀,

Nítorí pé ògo ilé rẹ̀ ń pọ̀ sí i,

17 Nítorí tí ó bá kú, kò lè mú ohunkóhun lọ;+

Ògo rẹ̀ kò ní bá a sọ̀ kalẹ̀ lọ.+

18 Nítorí nígbà ayé rẹ̀, ó ń yin ara* rẹ̀.+

(Aráyé máa ń yin èèyàn nígbà tó bá láásìkí.)+

19 Àmọ́ nígbẹ̀yìn, yóò dara pọ̀ mọ́ ìran àwọn baba ńlá rẹ̀.

Wọn kò ní rí ìmọ́lẹ̀ mọ́ láé.

20 Ẹni tí kò bá lóye èyí, bí a tilẹ̀ dá a lọ́lá,+

Kò sàn ju àwọn ẹranko tó ń ṣègbé.

Orin Ásáfù.+

50 Ọlọ́run àwọn ọlọ́run, Jèhófà,*+ ti sọ̀rọ̀;

Ó pe ayé

Láti yíyọ oòrùn títí dé wíwọ̀ rẹ̀.*

 2 Láti Síónì, tí ó ní ẹwà pípé,+ ni Ọlọ́run ti tàn jáde.

 3 Ọlọ́run wa yóò wá, kò sì ní dákẹ́.+

Iná tó ń jó nǹkan run wà níwájú rẹ̀,+

Ìjì tó lágbára sì ń jà ní gbogbo àyíká rẹ̀.+

 4 Ó pe ọ̀run lókè, ó sì pe ayé,+

Kí ó lè ṣèdájọ́ àwọn èèyàn rẹ̀,+ ó ní:

 5 “Ẹ kó àwọn ẹni ìdúróṣinṣin mi jọ sọ́dọ̀ mi,

Àwọn tí wọ́n fi ẹbọ bá mi dá májẹ̀mú.”+

 6 Àwọn ọ̀run ń kéde òdodo rẹ̀,

Nítorí Ọlọ́run fúnra rẹ̀ jẹ́ Onídàájọ́.+ (Sélà)

 7 “Ẹ fetí sílẹ̀, ẹ̀yin èèyàn mi, mo fẹ́ sọ̀rọ̀;

Ìwọ Ísírẹ́lì, màá ta kò ọ́.+

Èmi ni Ọlọ́run, àní Ọlọ́run rẹ.+

 8 Mi ò bá ọ wí nítorí àwọn ẹbọ rẹ

Tàbí nítorí àwọn odindi ẹbọ sísun rẹ tó wà níwájú mi nígbà gbogbo.+

 9 Mi ò nílò akọ màlúù láti ilé rẹ,

Bẹ́ẹ̀ ni mi ò nílò àwọn ewúrẹ́* látinú ọgbà ẹran rẹ.+

10 Nítorí pé tèmi ni gbogbo ẹran inú igbó,+

Títí kan àwọn ẹranko tó wà lórí gbogbo òkè.

11 Mo mọ gbogbo ẹyẹ tó wà lórí àwọn òkè;+

Àìlóǹkà àwọn ẹran tó wà nínú pápá jẹ́ tèmi.

12 Ká ní ebi ń pa mí, mi ò ní sọ fún ọ,

Nítorí ilẹ̀ eléso àti gbogbo ohun tó wà nínú rẹ̀ jẹ́ tèmi.+

13 Ṣé mo fẹ́ jẹ ẹran màlúù* ni

Àbí mo fẹ́ mu ẹ̀jẹ̀ òbúkọ?+

14 Rú ẹbọ ọpẹ́ sí Ọlọ́run,+

Kí o sì san ẹ̀jẹ́ rẹ fún Ẹni Gíga Jù Lọ;+

15 Pè mí ní àkókò wàhálà.+

Màá gbà ọ́ sílẹ̀, wàá sì máa yìn mí lógo.”+

16 Àmọ́ Ọlọ́run yóò sọ fún ẹni burúkú pé:

“Ẹ̀tọ́ wo lo ní láti máa sọ àwọn ìlànà mi+

Tàbí láti máa sọ nípa májẹ̀mú mi?+

17 Nítorí o kórìíra ìbáwí,*

O sì ń kọ ẹ̀yìn sí ọ̀rọ̀ mi.*+

18 Nígbà tí o rí olè, o tẹ́wọ́ gbà á,*+

O sì ń bá àwọn alágbèrè kẹ́gbẹ́.

19 Ò ń fi ẹnu rẹ sọ ohun búburú kiri,

Ẹ̀tàn sì wà lórí ahọ́n rẹ.+

20 O jókòó, o sì sọ̀rọ̀ tí kò dáa sí arákùnrin rẹ;+

O fi àléébù ọmọ ìyá rẹ hàn.*

21 Nígbà tí o ṣe àwọn nǹkan yìí, mi ò sọ̀rọ̀,

Torí náà, o rò pé màá dà bíi tìẹ.

Àmọ́ ní báyìí, màá bá ọ wí,

Màá sì pè ọ́ lẹ́jọ́.+

22 Ẹ jọ̀wọ́, ẹ rò ó wò ná, ẹ̀yin tí ẹ gbàgbé Ọlọ́run,+

Kí n má bàa fà yín ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ láìsí ẹni tó máa gbà yín sílẹ̀.

23 Ẹni tó mú ọpẹ́ wá, tí ó fi rúbọ sí mi ń yìn mí lógo,+

Ní ti ẹni tó sì ń rin ọ̀nà tí ó tọ́,

Màá mú kí ó rí ìgbàlà látọ̀dọ̀ mi.”+

Sí olùdarí. Orin Dáfídì, nígbà tí

wòlíì Nátánì wọlé wá bá a lẹ́yìn tí Dáfídì bá Bátí-ṣébà lò pọ̀.+

51 Ọlọ́run, ṣojú rere sí mi, nítorí ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀.+

Nu àwọn àṣìṣe mi kúrò nítorí ọ̀pọ̀ àánú rẹ.+

 2 Wẹ̀ mí mọ́ tónítóní kúrò nínú ìṣìnà mi,+

Kí o sì wẹ̀ mí mọ́ kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ mi.+

 3 Nítorí mo mọ àwọn àṣìṣe mi dáadáa,

Ẹ̀ṣẹ̀ mi sì wà níwájú mi* nígbà gbogbo.+

 4 Ìwọ gan-an* ni mo dẹ́ṣẹ̀ sí,+

Mo ti ṣe ohun tó burú ní ojú rẹ.+

Torí náà, olódodo ni ọ́ nígbà tí o bá ń sọ̀rọ̀,

Ìdájọ́ rẹ sì tọ́.+

 5 Wò ó! A bí mi ní ẹlẹ́ṣẹ̀,

Inú ẹ̀ṣẹ̀ sì ni ìyá mi* lóyún mi.+

 6 Wò ó! Inú rẹ máa ń dùn sí òtítọ́ tó ti ọ̀kan ẹni wá;+

Kọ́ inú mi lọ́hùn-ún* ní ọgbọ́n tòótọ́.

 7 Fi hísópù wẹ̀ mí mọ́ kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ mi, kí n lè mọ́;+

Wẹ̀ mí, kí n lè funfun ju yìnyín lọ.+

 8 Jẹ́ kí n gbọ́ ìró ayọ̀ àti ti ìdùnnú,

Kí àwọn egungun mi tí ìwọ ti fọ́ lè máa yọ̀.+

 9 Gbé ojú rẹ* kúrò lára àwọn ẹ̀ṣẹ̀ mi,+

Kí o sì pa gbogbo ìṣìnà mi rẹ́.*+

10 Dá ọkàn mímọ́ sí inú mi, Ọlọ́run,+

Kí o sì fi ẹ̀mí tuntun sí inú mi,+ èyí tó fìdí múlẹ̀.

11 Má ṣe gbé mi sọ nù kúrò níwájú rẹ;

Má sì gba ẹ̀mí mímọ́ rẹ kúrò lára mi.

12 Dá ayọ̀ ìgbàlà rẹ pa dà fún mi;+

Kí o sì jẹ́ kó máa wù mí láti ṣègbọràn sí ọ.*

13 Màá kọ́ àwọn arúfin ní àwọn ọ̀nà rẹ,+

Kí àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ lè pa dà sọ́dọ̀ rẹ.

14 Gbà mí lọ́wọ́ ẹ̀bi ẹ̀jẹ̀,+ ìwọ Ọlọ́run, Ọlọ́run ìgbàlà mi,+

Kí ahọ́n mi lè máa fi ìdùnnú kéde òdodo rẹ.+

15 Jèhófà, ṣí ètè mi,

Kí ẹnu mi lè máa kéde ìyìn rẹ.+

16 Nítorí kì í ṣe ẹbọ ni ìwọ fẹ́, ká ní bẹ́ẹ̀ ni, mi ò bá ti rú u,+

Kì í sì í ṣe odindi ẹbọ sísun ló ń mú inú rẹ dùn.+

17 Àwọn ẹbọ tó ń mú inú Ọlọ́run dùn ni ọkàn tó gbọgbẹ́;

Ìwọ Ọlọ́run, o kò ní pa ọkàn tó gbọgbẹ́ tó sì ní ìdààmú tì.*+

18 Ṣe ohun rere fún Síónì nítorí inú rere rẹ;

Mọ ògiri Jerúsálẹ́mù.

19 Nígbà náà, inú rẹ yóò máa dùn sí àwọn ẹbọ òdodo,

Àwọn ẹbọ sísun àti àwọn odindi ẹbọ;

A ó sì fi àwọn akọ màlúù rúbọ lórí pẹpẹ rẹ.+

Sí olùdarí. Másíkílì.* Ti Dáfídì, nígbà tí Dóẹ́gì ọmọ Édómù wá, tó sì sọ fún Sọ́ọ̀lù pé Dáfídì wá sí ilé Áhímélékì.+

52 Kí ló dé tí ò ń fi ìwà burúkú rẹ ṣògo, ìwọ alágbára ńlá?+

Ṣé o kò mọ̀ pé ìfẹ́ Ọlọ́run tí kì í yẹ̀ wà láti ọjọ́ dé ọjọ́ ni?+

 2 Ahọ́n rẹ mú bí abẹ fẹ́lẹ́,+

Ó ń pète ibi, ó sì ń ṣiṣẹ́ ẹ̀tàn.+

 3 Ìwọ nífẹ̀ẹ́ ohun búburú ju ohun rere lọ,

O sì nífẹ̀ẹ́ pípa irọ́ ju sísọ ohun tí ó tọ́. (Sélà)

 4 O nífẹ̀ẹ́ gbogbo ọ̀rọ̀ tó ń pani run,

Ìwọ ahọ́n ẹ̀tàn!

 5 Ìdí nìyẹn tí Ọlọ́run yóò fi mú ọ balẹ̀ láìtún gbérí mọ́;+

Yóò gbá ọ mú, yóò sì fà ọ́ kúrò nínú àgọ́ rẹ;+

Yóò fà ọ́ tu kúrò ní ilẹ̀ alààyè.+ (Sélà)

 6 Àwọn olódodo á rí i, ẹnu á yà wọ́n,+

Wọ́n á sì fi í rẹ́rìn-ín.+

 7 “Ọkùnrin yìí kò fi Ọlọ́run ṣe ibi ààbò* rẹ̀,+

Àmọ́ ó gbẹ́kẹ̀ lé ọ̀pọ̀ ọrọ̀ tó ní,+

Èrò ibi tó wà lọ́kàn rẹ̀* ló sì gbára lé.”*

 8 Ṣùgbọ́n màá dà bí igi ólífì tó gbẹ̀rẹ̀gẹ̀jigẹ̀ nínú ilé Ọlọ́run;

Ìfẹ́ Ọlọ́run tí kì í yẹ̀ ni mo gbẹ́kẹ̀ lé+ títí láé àti láéláé.

 9 Èmi yóò máa yìn ọ́ títí láé torí pé o ti gbé ìgbésẹ̀;+

Níwájú àwọn ẹni ìdúróṣinṣin rẹ,

Màá gbẹ́kẹ̀ lé orúkọ rẹ,+ nítorí ó dára.

Sí olùdarí; lọ́nà ti Máhálátì.* Másíkílì.* Ti Dáfídì.

53 Òmùgọ̀* sọ lọ́kàn rẹ̀ pé:

“Kò sí Jèhófà.”+

Ìwà àìtọ́ wọn burú, ó sì jẹ́ ohun ìríra;

Kò sí ẹni tó ń ṣe rere.+

 2 Àmọ́ Ọlọ́run ń bojú wo àwọn ọmọ èèyàn láti ọ̀run+

Láti rí i bóyá ẹnì kan wà tó ní ìjìnlẹ̀ òye, bóyá ẹnì kan wà tó ń wá Jèhófà.+

 3 Gbogbo wọn ti kúrò lójú ọ̀nà;

Gbogbo wọn jẹ́ oníwà ìbàjẹ́.

Kò sí ẹni tó ń ṣe rere,

Kò tiẹ̀ sí ẹyọ kan.+

 4 Ṣé kò yé ìkankan lára àwọn oníwà burúkú ni?

Wọ́n ń ya àwọn èèyàn mi jẹ bí ẹni ń jẹ búrẹ́dì.

Wọn ò ké pe Jèhófà.+

 5 Àmọ́, jìnnìjìnnì á bò wọ́n,

Irú èyí tí kò ṣẹlẹ̀ sí wọn rí,*

Ọlọ́run yóò tú egungun àwọn tó ń gbéjà kò ọ́* ká.

Wàá dójú tì wọ́n, nítorí Jèhófà ti kọ̀ wọ́n sílẹ̀.

 6 Ká ní ìgbàlà Ísírẹ́lì lè wá láti Síónì ni!+

Nígbà tí Jèhófà bá kó àwọn èèyàn rẹ̀ tó wà lóko ẹrú pa dà,

Kí inú Jékọ́bù dùn, kí Ísírẹ́lì sì yọ̀.

Sí olùdarí; kí a kọ ọ́ pẹ̀lú àwọn ohun ìkọrin olókùn tín-ín-rín. Másíkílì.* Ti Dáfídì, nígbà tí àwọn ọmọ Sífù wá sọ́dọ̀ Sọ́ọ̀lù, tí wọ́n sì sọ fún un pé: “Àárín wa ni Dáfídì fara pa mọ́ sí.”+

54 Ọlọ́run, fi orúkọ rẹ gbà mí,+

Sì fi agbára rẹ gbèjà mi.*+

 2 Ọlọ́run, gbọ́ àdúrà mi;+

Fetí sí ọ̀rọ̀ ẹnu mi.

 3 Nítorí àwọn àjèjì dìde sí mi,

Àwọn ìkà ẹ̀dá sì ń wá ẹ̀mí* mi.+

Wọn ò ka Ọlọ́run sí.*+ (Sélà)

 4 Wò ó! Ọlọ́run ni olùrànlọ́wọ́ mi;+

Jèhófà wà pẹ̀lú àwọn tó ń tì mí* lẹ́yìn.

 5 Yóò san ìwà ìkà àwọn ọ̀tá mi pa dà fún wọn;+

Pa wọ́n run* nínú òtítọ́ rẹ.+

 6 Màá rúbọ sí ọ+ tinútinú.

Màá yin orúkọ rẹ, Jèhófà, nítorí ó dára.+

 7 Nítorí o gbà mí nínú gbogbo wàhálà,+

Màá sì máa wo ìṣubú àwọn ọ̀tá mi.+

Sí olùdarí; kí a kọ ọ́ pẹ̀lú àwọn ohun ìkọrin olókùn tín-ín-rín. Másíkílì.* Ti Dáfídì.

55 Gbọ́ àdúrà mi, Ọlọ́run,+

Má sì ṣàìka ẹ̀bẹ̀ àánú mi sí.*+

 2 Fiyè sí mi, kí o sì dá mi lóhùn.+

Àníyàn mi ò jẹ́ kí n ní ìsinmi,+

Ọkàn mi ò sì balẹ̀

 3 Nítorí ohun tí ọ̀tá ń sọ

Àti bí ẹni burúkú ṣe ń dà mí láàmú.

Wọ́n ń rọ̀jò wàhálà lé mi lórí,

Wọ́n sì dì mí sínú torí pé wọ́n ń bínú mi.+

 4 Ọkàn mi ń jẹ̀rora nínú mi,+

Jìnnìjìnnì ikú sì bò mí.+

 5 Ìbẹ̀rù àti ìwárìrì dé bá mi,

Gbogbo ara mi sì ń gbọ̀n pẹ̀pẹ̀.

 6 Mò ń sọ pé: “Ká ní mo ní ìyẹ́ apá bí àdàbà ni!

Mi ò bá fò lọ, mi ò bá sì máa gbé lábẹ́ ààbò.

 7 Wò ó! Màá lọ jìnnà réré.+

Màá lọ máa gbé inú aginjù.+ (Sélà)

 8 Màá yára lọ sí ibi tó láàbò

Kúrò lọ́wọ́ ẹ̀fúùfù líle àti kúrò lọ́wọ́ ìjì.”

 9 Da èrò wọn rú, Jèhófà, sì mú kí èrò wọn já sófo,*+

Nítorí mo ti rí ìwà ipá àti ìjà nínú ìlú náà.

10 Tọ̀sántòru ni wọ́n ń rìn kiri lórí ògiri rẹ̀;

Èrò ibi àti ìjàngbọ̀n ló wà nínú rẹ̀.+

11 Ìparun wà nínú rẹ̀;

Ìnilára àti ẹ̀tàn kì í kúrò ní ojúde rẹ̀.+

12 Kì í ṣe ọ̀tá ló ń pẹ̀gàn mi;+

Tó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, mi ò bá fara dà á.

Kì í ṣe elénìní ló dìde sí mi;

Tó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, mi ò bá sá pa mọ́ fún un.

13 Àmọ́ ìwọ ni, èèyàn bíi tèmi,*+

Alábàákẹ́gbẹ́ mi tí mo mọ̀ dáadáa.+

14 Ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ ni wá tẹ́lẹ̀, a sì gbádùn ọ̀rẹ́ wa;

A máa ń bá ọ̀pọ̀ èèyàn rìn lọ sí ilé Ọlọ́run.

15 Kí ìparun dé bá wọn!+

Kí wọ́n wọnú Isà Òkú* láàyè;

Nítorí ìwà ibi wà láàárín wọn, ó sì ń gbé inú wọn.

16 Ní tèmi, màá ké pe Ọlọ́run,

Jèhófà yóò sì gbà mí sílẹ̀.+

17 Ní alẹ́, ní òwúrọ̀ àti ní ọ̀sán, ìdààmú bá mi, mò ń kérora,*+

Ó sì ń gbọ́ ohùn mi.+

18 Yóò gbà mí sílẹ̀* lọ́wọ́ àwọn tó ń bá mi jà, yóò sì jẹ́ kí n* ní àlàáfíà,

Nítorí ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ èèyàn ló ń gbéjà kò mí.+

19 Ọlọ́run yóò gbọ́, yóò sì fún wọn lésì,+

Ẹni tó ti ń jókòó lórí ìtẹ́ tipẹ́tipẹ́.+ (Sélà)

Wọn ò ní yí pa dà,

Àwọn tí kò bẹ̀rù Ọlọ́run.+

20 Ó* gbéjà ko àwọn tó wà ní àlàáfíà pẹ̀lú rẹ̀;+

Ó da májẹ̀mú rẹ̀.+

21 Ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ̀ jọ̀lọ̀ ju bọ́tà lọ,+

Àmọ́ ìjà ló wà lọ́kàn rẹ̀.

Ọ̀rọ̀ rẹ̀ tuni lára ju òróró lọ,

Àmọ́ idà tí a fà yọ ni wọ́n.+

22 Ju ẹrù rẹ sọ́dọ̀ Jèhófà,+

Yóò sì gbé ọ ró.+

Kò ní jẹ́ kí olódodo ṣubú* láé.+

23 Àmọ́ ìwọ, Ọlọ́run, yóò rẹ̀ wọ́n wálẹ̀ sínú kòtò tó jìn jù lọ.+

Àwọn tó jẹ̀bi ẹ̀jẹ̀, tí wọ́n sì jẹ́ ẹlẹ́tàn kò ní lo ààbọ̀ ọjọ́ ayé wọn.+

Àmọ́ ní tèmi, màá gbẹ́kẹ̀ lé ọ.

Sí olùdarí; kí a yí i sí “Àdàbà Tó Dákẹ́ Tó Jìnnà Réré.” Ti Dáfídì. Míkítámù.* Nígbà tí àwọn Filísínì mú un ní Gátì.+

56 Ṣojú rere sí mi, Ọlọ́run, nítorí ẹni kíkú ń gbéjà kò mí.*

Láti àárọ̀ ṣúlẹ̀, wọ́n ń bá mi jà, wọ́n sì ń ni mí lára.

 2 Àwọn ọ̀tá mi ń kù gìrì mọ́ mi láti àárọ̀ ṣúlẹ̀;

Ọ̀pọ̀ èèyàn ló ń gbéra ga sí mi, tí wọ́n sì ń bá mi jà.

 3 Nígbà tí ẹ̀rù ń bà mí,+ mo gbẹ́kẹ̀ lé ọ.+

 4 Ìwọ Ọlọ́run, ẹni tí mò ń yin ọ̀rọ̀ rẹ̀,

Ìwọ ni mo gbẹ́kẹ̀ lé; ẹ̀rù ò bà mí.

Kí ni èèyàn* lásánlàsàn lè fi mí ṣe?+

 5 Láti àárọ̀ ṣúlẹ̀, wọn ò jẹ́ kí n gbádùn ayé mi;

Bí wọ́n ṣe máa ṣe mí léṣe ni wọ́n ń rò ṣáá.+

 6 Wọ́n fara pa mọ́ láti gbéjà kò mí;

Wọ́n ń ṣọ́ gbogbo ìrìn ẹsẹ̀ mi,+

Kí wọ́n lè gba ẹ̀mí mi.*+

 7 Kọ̀ wọ́n sílẹ̀ nítorí ìwà ìkà wọn.

Mú àwọn orílẹ̀-èdè balẹ̀ nínú ìbínú rẹ, Ọlọ́run.+

 8 Ò ń kíyè sí bí mo ṣe ń rìn kiri.+

Gba omijé mi sínú ìgò awọ rẹ.+

Ǹjẹ́ kò wà lákọsílẹ̀ nínú ìwé rẹ?+

 9 Àwọn ọ̀tá mi á sá pa dà ní ọjọ́ tí mo bá ké pè ọ́ fún ìrànlọ́wọ́.+

Ó dá mi lójú pé: Ọlọ́run wà pẹ̀lú mi.+

10 Ìwọ Ọlọ́run, ẹni tí mò ń yin ọ̀rọ̀ rẹ̀,

Ìwọ Jèhófà, ẹni tí mò ń yin ọ̀rọ̀ rẹ̀,

11 Ìwọ Ọlọ́run ni mo gbẹ́kẹ̀ lé; ẹ̀rù ò bà mí.+

Kí ni èèyàn lásánlàsàn lè fi mí ṣe?+

12 Ọlọ́run, ẹ̀jẹ́ tí mo jẹ́ fún ọ dè mí;+

Màá rú ẹbọ ọpẹ́ sí ọ.+

13 Nítorí pé o ti gbà mí* lọ́wọ́ ikú,+

O ò sì jẹ́ kí n fẹsẹ̀ kọ,+

Kí n lè máa rìn níwájú Ọlọ́run nínú ìmọ́lẹ̀ alààyè.+

Sí olùdarí; kí a yí i sí “Má Ṣe Pa Á Run.” Ti Dáfídì. Míkítámù.* Nígbà tó sá nítorí Sọ́ọ̀lù, tó sì lọ sínú ihò àpáta.+

57 Ṣojú rere sí mi, Ọlọ́run, ṣojú rere sí mi,

Nítorí ìwọ ni mo* fi ṣe ibi ààbò,+

Abẹ́ òjìji ìyẹ́ apá rẹ sì ni mo sá sí títí wàhálà fi kọjá lọ.+

 2 Mo ké pe Ọlọ́run, Ẹni Gíga Jù Lọ,

Ọlọ́run tòótọ́, ẹni tó bá mi pa wọ́n rẹ́.

 3 Yóò pèsè ìrànlọ́wọ́ láti ọ̀run, yóò sì gbà mí là.+

Yóò mú kí ìsapá ẹni tó ń kù gìrì mọ́ mi já sí asán. (Sélà)

Ọlọ́run yóò fi ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ àti òtítọ́ rẹ̀ ránṣẹ́.+

 4 Àwọn kìnnìún yí mi* ká;+

Àárín àwọn tó fẹ́ fà mí ya ni mo dùbúlẹ̀ sí,

Àwọn tí eyín wọn jẹ́ ọ̀kọ̀ àti ọfà,

Tí ahọ́n wọn sì jẹ́ idà mímú.+

 5 Kí a gbé ọ ga ju ọ̀run lọ, ìwọ Ọlọ́run;

Kí ògo rẹ wà lórí gbogbo ayé.+

 6 Wọ́n ti dẹ àwọ̀n láti fi mú ẹsẹ̀ mi;+

Ìdààmú dorí mi* kodò.+

Wọ́n ti gbẹ́ kòtò dè mí,

Àmọ́ àwọn fúnra wọn kó sínú rẹ̀.+ (Sélà)

 7 Ọkàn mi dúró ṣinṣin, Ọlọ́run,+

Ọkàn mi dúró ṣinṣin.

Màá kọrin, màá sì lo ohun ìkọrin.

 8 Jí, ìwọ ògo mi.

Jí, ìwọ ohun ìkọrin olókùn tín-ín-rín; àti ìwọ náà, háàpù.

Màá jí ní kùtùkùtù.+

 9 Jèhófà, màá yìn ọ́ láàárín àwọn èèyàn;+

Màá fi orin yìn ọ́* láàárín àwọn orílẹ̀-èdè.+

10 Nítorí ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ ga gan-an, ó dé ọ̀run,+

Òtítọ́ rẹ sì ga dé sánmà.

11 Kí a gbé ọ ga ju ọ̀run lọ, ìwọ Ọlọ́run;

Kí ògo rẹ wà lórí gbogbo ayé.+

Sí olùdarí; kí a yí i sí “Má Ṣe Pa Á Run.” Ti Dáfídì. Míkítámù.*

58 Ṣé ẹ lè sọ nípa òdodo nígbà tó jẹ́ pé ńṣe lẹ dákẹ́?+

Ṣé ẹ lè fi òdodo ṣe ìdájọ́, ẹ̀yin ọmọ èèyàn?+

 2 Kàkà bẹ́ẹ̀, ẹ̀ ń hùmọ̀ àìṣòdodo nínú ọkàn yín,+

Ọwọ́ yín sì ń gbé ìwà ipá jáde ní ilẹ̀ náà.+

 3 Àwọn ẹni burúkú ti ṣìnà* látìgbà tí wọ́n ti bí wọn;*

Oníwàkiwà ni wọ́n, òpùrọ́ sì ni wọ́n látìgbà tí wọ́n ti bí wọn.

 4 Oró wọ́n dà bí oró ejò;+

Wọ́n jẹ́ adití bí ejò ṣèbé tó di etí rẹ̀.

 5 Kì í fetí sí ohùn àwọn atujú,

Kò sí bí wọ́n ṣe mọ ọfọ̀ pè tó.

 6 Ọlọ́run, gbá eyín wọn yọ kúrò lẹ́nu wọn!

Fọ́ páárì ẹ̀rẹ̀kẹ́ àwọn kìnnìún yìí,* Jèhófà!

 7 Kí wọ́n pòórá bí ìgbà tí omi bá gbẹ.

Kí Ó tẹ ọrun rẹ̀, kí ọfà rẹ̀ sì mú kí wọ́n ṣubú.

 8 Kí wọ́n dà bí ìgbín tó ń yọ́ dà nù bó ṣe ń lọ;

Bí ọmọ tí obìnrin kan bí ní òkú, tí kò rí oòrùn.

 9 Kí àwọn ìkòkò oúnjẹ yín tó mọ iná igi ẹlẹ́gùn-ún lára,

Ọlọ́run yóò gbá ẹ̀ka tútù àti èyí tó ń jó, bí ìgbà tí ìjì bá gbá nǹkan dà nù.+

10 Olódodo yóò máa yọ̀ nítorí pé ó ti rí ẹ̀san;+

Ẹ̀jẹ̀ ẹni burúkú yóò rin ẹsẹ̀ rẹ̀ gbingbin.+

11 Nígbà náà, aráyé á sọ pé: “Dájúdájú, èrè wà fún olódodo.+

Ní tòótọ́, Ọlọ́run kan wà tó ń ṣe ìdájọ́ ayé.”+

Sí olùdarí; kí a yí i sí “Má Ṣe Pa Á Run.” Ti Dáfídì. Míkítámù.* Nígbà tí Sọ́ọ̀lù rán àwọn èèyàn pé kí wọ́n lọ máa ṣọ́ ilé Dáfídì* kí ó lè pa á.+

59 Ọlọ́run mi, gbà mí lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá mi;+

Dáàbò bò mí lọ́wọ́ àwọn tó ń dìde sí mi.+

 2 Gbà mí lọ́wọ́ àwọn tó ń hùwà burúkú,

Kí o sì gbà mí sílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn oníwà ipá.*

 3 Wò ó! wọ́n lúgọ dè mí;*+

Àwọn alágbára gbéjà kò mí

Àmọ́ Jèhófà, kì í ṣe torí pé mo ṣọ̀tẹ̀ tàbí pé mo dẹ́ṣẹ̀.+

 4 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé mi ò ṣe ohun tí kò dáa, wọ́n sáré múra sílẹ̀ láti bá mi jà.

Dìde nígbà tí mo bá pè, kí o sì wò mí.

 5 Nítorí ìwọ, Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun ni Ọlọ́run Ísírẹ́lì.+

Jí láti yí àfiyèsí rẹ sí gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè.

Má ṣe ṣàánú ẹnikẹ́ni tó jẹ́ ọ̀dàlẹ̀ abatẹnijẹ́.+ (Sélà)

 6 Wọ́n ń wá ní ìrọ̀lẹ́ ìrọ̀lẹ́;+

Wọ́n ń kùn* bí ajá,+ wọ́n sì ń dọdẹ kiri ìlú.+

 7 Wo ohun tó ń tú* jáde lẹ́nu wọn;

Ètè wọn dà bí idà,+

Wọ́n ń sọ pé: “Ta ló ń gbọ́ wa?”+

 8 Àmọ́ ìwọ, Jèhófà, yóò fi wọ́n rẹ́rìn-ín;+

Wàá fi gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè ṣẹ̀sín.+

 9 Ìwọ Okun mi, ìwọ ni èmi yóò máa wò;+

Nítorí Ọlọ́run ni ibi ààbò mi.*+

10 Ọlọ́run tó ń fi ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ hàn sí mi yóò ràn mí lọ́wọ́;+

Ọlọ́run yóò mú kí n rí ìṣubú àwọn ọ̀tá mi.+

11 Má pa wọ́n, kí àwọn èèyàn mi má bàa gbàgbé.

Fi agbára rẹ mú kí wọ́n máa rìn gbéregbère;

Mú kí wọ́n ṣubú, ìwọ Jèhófà, apata wa.+

12 Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ tó wà lẹ́nu wọn àti ọ̀rọ̀ ètè wọn,

Kí ìgbéraga wọn dẹkùn mú wọn,+

Nítorí ègún àti ẹ̀tàn tí wọ́n ń sọ lẹ́nu.

13 Yanjú wọn nínú ìbínú rẹ;+

Yanjú wọn, kí wọ́n má bàa sí mọ́;

Jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé Ọlọ́run ń ṣàkóso ní Jékọ́bù títí dé gbogbo ìkángun ayé.+ (Sélà)

14 Jẹ́ kí wọ́n pa dà wá ní ìrọ̀lẹ́;

Jẹ́ kí wọ́n máa kùn* bí ajá, kí wọ́n sì máa dọdẹ kiri ìlú.+

15 Jẹ́ kí wọ́n máa wá ohun tí wọ́n á jẹ kiri;+

Má ṣe jẹ́ kí wọ́n yó tàbí kí wọ́n rí ibi sùn.

16 Àmọ́ ní tèmi, màá kọrin nípa okun rẹ;+

Ní àárọ̀, màá fi ìdùnnú sọ nípa ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀.

Nítorí ìwọ ni ibi ààbò mi+

Àti ibi tí mo lè sá sí ní ọjọ́ wàhálà mi.+

17 Ìwọ Okun mi, ìwọ ni màá fi orin yìn,*+

Nítorí Ọlọ́run ni ibi ààbò mi, Ọlọ́run tó ń fi ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ hàn sí mi.+

Sí olùdarí; kí a yí i sí “Òdòdó Lílì Ìránnilétí.” Míkítámù.* Ti Dáfídì. Fún kíkọ́ni. Nígbà tó bá Aramu-náháráímù àti Aramu-Sóbà jà, tí Jóábù sì pa dà lọ pa 12,000 àwọn ọmọ Édómù ní Àfonífojì Iyọ̀.+

60 Ọlọ́run, o ti pa wá tì; o ti ya ààbò wa lulẹ̀.+

O bínú sí wa; àmọ́ ní báyìí, gbà wá pa dà!

 2 O mú kí ilẹ̀ ayé mì tìtì; o mú kí ó lanu.

Dí àwọn àlàfo rẹ̀, torí ó ti ń wó.

 3 O mú kí ìyà jẹ àwọn èèyàn rẹ.

O mú kí a mu wáìnì tó ń mú wa ta gbọ̀n-ọ́n gbọ̀n-ọ́n.+

 4 Fún* àwọn tó bẹ̀rù rẹ ní àmì

Kí wọ́n lè sá, kí wọ́n sì yẹ ọfà.* (Sélà)

 5 Kí a lè gba àwọn olùfẹ́ rẹ sílẹ̀,

Fi ọwọ́ ọ̀tún rẹ gbà wá sílẹ̀, kí o sì dá wa lóhùn.+

 6 Ọlọ́run ti sọ̀rọ̀ nínú ìjẹ́mímọ́* rẹ̀ pé:

“Màá yọ ayọ̀ ìṣẹ́gun, màá fi Ṣékémù ṣe ogún fún àwọn èèyàn mi,+

Màá sì díwọ̀n Àfonífojì* Súkótù fún ẹni tí mo bá fẹ́.+

 7 Gílíádì jẹ́ tèmi, bí Mánásè ṣe jẹ́ tèmi,+

Éfúrémù sì ni akoto* orí mi;

Júdà ni ọ̀pá àṣẹ mi.+

 8 Móábù ni bàsíà tí mo fi ń wẹ ẹsẹ̀.+

Orí Édómù ni màá ju bàtà mi sí.+

Màá kígbe ìṣẹ́gun lórí Filísíà.”+

 9 Ta ló máa mú mi wá sí ìlú tí a dó tì?*

Ta ló máa mú mi lọ sí Édómù?+

10 Ìwọ Ọlọ́run tí o ti kọ̀ wá sílẹ̀ náà ni,

Ìwọ Ọlọ́run wa, tí o kò bá àwọn ọmọ ogun wa jáde mọ́.+

11 Ràn wá lọ́wọ́ nínú wàhálà wa,

Nítorí asán ni ìgbàlà látọwọ́ èèyàn.+

12 Ọlọ́run ló máa fún wa lágbára,+

Yóò sì tẹ àwọn ọ̀tá wa rẹ́.+

Sí olùdarí; kí a kọ ọ́ pẹ̀lú àwọn ohun ìkọrin olókùn tín-ín-rín. Ti Dáfídì.

61 Ọlọ́run, gbọ́ igbe ìrànlọ́wọ́ mi.

Fetí sí àdúrà mi.+

 2 Màá ké pè ọ́ láti ìkángun ayé

Nígbà tí ìrẹ̀wẹ̀sì bá bá* ọkàn mi.+

Darí mi lọ sórí àpáta tó ga jù mí lọ.+

 3 Nítorí ìwọ ni ibi ààbò mi,

Ilé gogoro alágbára tó ń dáàbò bò mí lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá.+

 4 Màá wà* nínú àgọ́ rẹ títí láé;+

Màá fi abẹ́ ìyẹ́ apá rẹ ṣe ibi ààbò.+ (Sélà)

 5 Nítorí ìwọ, Ọlọ́run, ti gbọ́ àwọn ẹ̀jẹ́ mi.

O ti fún mi ní ogún tó jẹ́ ti àwọn tó bẹ̀rù orúkọ rẹ.+

 6 Wàá mú kí ẹ̀mí ọba gùn,*+

Àwọn ọdún rẹ̀ yóò sì jẹ́ láti ìran dé ìran.

 7 Yóò jókòó lórí ìtẹ́* níwájú Ọlọ́run títí láé;+

Fún un ní ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ àti òtítọ́,* kí wọ́n lè máa dáàbò bò ó.+

 8 Nígbà náà, màá fi orin yin* orúkọ rẹ títí láé+

Bí mo ṣe ń san àwọn ẹ̀jẹ́ mi láti ọjọ́ dé ọjọ́.+

Sí olùdarí; ti Jédútúnì.* Orin Dáfídì.

62 Ní tòótọ́, mo* dúró jẹ́ẹ́ de Ọlọ́run.

Ọ̀dọ̀ rẹ̀ ni ìgbàlà mi ti wá.+

 2 Ní tòótọ́, òun ni àpáta mi àti ìgbàlà mi, ibi ààbò mi;*+

Mìmì kan ò ní mì mí débi tí màá ṣubú.+

 3 Ìgbà wo lẹ máa kọ lu ọkùnrin kan dà kí ẹ lè pa á?+

Gbogbo yín léwu bí ògiri tó dagun, ògiri olókùúta tó ti fẹ́ wó.*

 4 Nítorí wọ́n gbìmọ̀ pọ̀ láti taari rẹ̀ kúrò ní ipò gíga tó wà;*

Wọ́n fẹ́ràn láti máa parọ́.

Wọ́n ń fi ẹnu wọn súre, àmọ́ nínú wọn lọ́hùn-ún, wọ́n ń gégùn-ún.+ (Sélà)

 5 Ní tòótọ́, mo* dúró jẹ́ẹ́ de Ọlọ́run+

Nítorí pé ọ̀dọ̀ rẹ̀ ni ìrètí mi ti wá.+

 6 Ní tòótọ́, òun ni àpáta mi àti ìgbàlà mi, ibi ààbò mi;

Mìmì kan ò ní mì mí.+

 7 Ọwọ́ Ọlọ́run ni ìgbàlà mi àti ògo mi wà.

Ọlọ́run ni àpáta lílágbára àti ibi ààbò mi.+

 8 Ẹ gbẹ́kẹ̀ lé e ní gbogbo ìgbà.

Ẹ tú ọkàn yín jáde níwájú rẹ̀.+

Ọlọ́run jẹ́ ibi ààbò fún wa.+ (Sélà)

 9 Èémí lásán ni àwọn ọmọ èèyàn,

Ẹ̀tàn ni àwọn ọmọ aráyé.+

Tí a bá gbé gbogbo wọn lórí òṣùwọ̀n, wọ́n fúyẹ́ ju èémí lásán.+

10 Ẹ má rò pé lílọ́ni lọ́wọ́ gbà máa mú kí ẹ ṣàṣeyọrí,

Ẹ má sì rò pé olè jíjà máa ṣe yín láǹfààní.

Tí ọrọ̀ yín bá ń pọ̀ sí i, ẹ má ṣe gbọ́kàn lé e.+

11 Ọlọ́run sọ̀rọ̀, mo sì gbọ́ lẹ́ẹ̀mejì:

Pé agbára jẹ́ ti Ọlọ́run.+

12 Bákan náà, ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ jẹ́ tìrẹ, Jèhófà,+

Nítorí o máa ń san kálukú lẹ́san iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀.+

Orin Dáfídì, nígbà tó wà ní aginjù Júdà.+

63 Ọlọ́run, ìwọ ni Ọlọ́run mi, mò ń wá ọ.+

Ọkàn mi ń fà sí ọ.*+

Àárẹ̀ ti mú mi* nítorí bó ṣe ń wù mí láti rí ọ

Ní ilẹ̀ tó gbẹ táútáú, níbi tí kò sí omi.+

 2 Torí náà, mo wò ọ́ ní ibi mímọ́;

Mo rí agbára rẹ àti ògo rẹ.+

 3 Nítorí ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ sàn ju ìyè,+

Ètè mi yóò máa yìn ọ́ lógo.+

 4 Torí náà, èmi yóò máa yìn ọ́ ní gbogbo ọjọ́ ayé mi;

Èmi yóò máa gbé ọwọ́ mi sókè ní orúkọ rẹ.

 5 Ìpín tó dára jù lọ, tó sì ṣeyebíye jù lọ la fi tẹ́ mi* lọ́rùn,*

Torí náà, ẹnu mi yóò yìn ọ́, ètè mi yóò sì kọrin.+

 6 Mo rántí rẹ lórí ibùsùn mi;

Mò ń ṣe àṣàrò nípa rẹ nígbà ìṣọ́ òru.+

 7 Nítorí ìwọ ni olùrànlọ́wọ́ mi,+

Mo sì ń kígbe ayọ̀ lábẹ́ òjìji ìyẹ́ apá rẹ.+

 8 Mo* rọ̀ mọ́ ọ;

Ọwọ́ ọ̀tún rẹ dì mí mú ṣinṣin.+

 9 Àmọ́ àwọn tó fẹ́ gba ẹ̀mí mi*

Yóò jìn sínú kòtò ikú.

10 A ó fi wọ́n fún idà,

Wọ́n á sì di oúnjẹ fún àwọn ajáko.*

11 Àmọ́ ọba yóò máa yọ̀ nínú Ọlọ́run.

Gbogbo ẹni tó ń fi Í búra yóò máa yìn Ín,*

Nítorí a ó pa àwọn tó ń parọ́ lẹ́nu mọ́.

Sí olùdarí. Orin Dáfídì.

64 Gbọ́ ohùn mi Ọlọ́run, bí mo ṣe ń bẹ̀bẹ̀.+

Yọ mí nínú ìbẹ̀rù ọ̀tá.

 2 Dáàbò bò mí lọ́wọ́ ohun tí àwọn ẹni ibi ń gbèrò ní ìkọ̀kọ̀,+

Lọ́wọ́ àwùjọ àwọn aṣebi.

 3 Wọ́n pọ́n ahọ́n wọn bí idà;

Wọ́n dojú ọ̀rọ̀ burúkú wọn kọni bí ọfà,

 4 Kí wọ́n lè ta aláìlẹ́bi lọ́fà láti ibi tí wọ́n fara pa mọ́ sí;

Wọ́n ta á lọ́fà lójijì, láìbẹ̀rù.

 5 Wọn ò jáwọ́ nínú èrò ibi wọn;*

Wọ́n sọ bí wọ́n ṣe máa dẹ pańpẹ́ wọn pa mọ́.

Wọ́n sọ pé: “Ta ló máa rí wọn?”+

 6 Wọ́n ń wá ọ̀nà tuntun láti ṣe ohun tí kò tọ́;

Wọ́n ń hùmọ̀ ọgbọ́n àlùmọ̀kọ́rọ́yí wọn ní ìkọ̀kọ̀;+

Inú kálukú wọn jìn.

 7 Àmọ́ Ọlọ́run yóò ta wọ́n lọ́fà;+

Ọfà yóò dọ́gbẹ́ sí wọn lára lójijì,

 8 Ahọ́n àwọn fúnra wọn yóò mú kí wọ́n ṣubú;+

Gbogbo àwọn tó ń wò wọ́n yóò mi orí.

 9 Nígbà náà, ẹ̀rù á ba gbogbo èèyàn,

Wọ́n á máa kéde ohun tí Ọlọ́run ti ṣe,

Wọ́n á sì lóye àwọn iṣẹ́ rẹ̀ jinlẹ̀.+

10 Olódodo á máa yọ̀ nínú Jèhófà, á sì fi í ṣe ibi ààbò rẹ̀;+

Gbogbo àwọn tí ọkàn wọn dúró ṣinṣin á máa ṣògo.*

Sí olùdarí. Orin Dáfídì. Orin.

65 Ọlọ́run, ìyìn ń dúró dè ọ́ ní Síónì;+

A ó san ẹ̀jẹ́ wa fún ọ.+

 2 Ìwọ Olùgbọ́ àdúrà, ọ̀dọ̀ rẹ ni onírúurú èèyàn* yóò wá.+

 3 Àwọn àṣìṣe mi ti bò mí mọ́lẹ̀,+

Àmọ́, o dárí àwọn ìṣìnà wa jì wá.+

 4 Aláyọ̀ ni ẹni tí o yàn, tí o sì mú wá sọ́dọ̀ rẹ

Kí ó lè máa gbé inú àwọn àgbàlá rẹ.+

Àwọn ohun rere inú ilé rẹ yóò tẹ́ wa lọ́rùn,+

Ìyẹn àwọn ohun inú tẹ́ńpìlì mímọ́* rẹ.+

 5 Wàá fi àwọn iṣẹ́ òdodo tó jẹ́ àgbàyanu dá wa lóhùn,+

Ìwọ Ọlọ́run ìgbàlà wa;

Ìwọ ni Ìgbẹ́kẹ̀lé gbogbo ayé+

Àti ti àwọn tó jìnnà réré lórí òkun.

 6 O* fìdí àwọn òkè múlẹ̀ ṣinṣin nípasẹ̀ agbára rẹ;

O* gbé agbára ńlá wọ̀ bí aṣọ.+

 7 O* mú kí àwọn òkun tó ń ru gùdù rọlẹ̀+

Pẹ̀lú ariwo ìgbì wọn àti rúkèrúdò àwọn orílẹ̀-èdè.+

 8 Àwọn iṣẹ́ àmì rẹ yóò mú kí ẹ̀rù rẹ ba àwọn tó ń gbé ibi tó jìnnà;+

Wàá mú kí àwọn tó wà ní ìlà oòrùn títí dé ìwọ̀ oòrùn kígbe ayọ̀.

 9 Ò ń bójú tó ayé,

O mú kí ó ní ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ èso,* kí ilẹ̀ rẹ̀ sì lọ́ràá dáadáa.+

Omi kún inú odò Ọlọ́run;

O pèsè oúnjẹ* fún wọn,+

Nítorí bí o ṣe ṣètò ayé nìyẹn.

10 O fi omi rin àwọn poro* rẹ̀, o sì mú kí ilẹ̀ rẹ̀ tí a tú* tẹ́jú;

O fi ọ̀wààrà òjò mú un dẹ̀; o mú kí ọ̀gbìn rẹ̀ dàgbà.+

11 O fi oore rẹ dé ọdún ládé;

Àwọn ohun rere kún ojú ọ̀nà rẹ rẹpẹtẹ.*+

12 Àwọn ibi ìjẹko tó wà ní aginjù kún,*+

Àwọn òkè kéékèèké gbé ìdùnnú wọ̀ bí aṣọ.+

13 Àwọn agbo ẹran bo ibi ìjẹko,

Ọkà sì bo àwọn àfonífojì.*+

Wọ́n ń kígbe ìṣẹ́gun, bẹ́ẹ̀ ni, wọ́n ń kọrin.+

Sí olùdarí. Orin. Orin atunilára.

66 Gbogbo ayé, ẹ kígbe ìṣẹ́gun sí Ọlọ́run.+

 2 Ẹ fi orin yin* orúkọ rẹ̀ ológo.

Ẹ mú kí ìyìn rẹ̀ ní ògo.+

 3 Ẹ sọ fún Ọlọ́run pé: “Àwọn iṣẹ́ rẹ mà bani lẹ́rù o!+

Nítorí agbára ńlá rẹ,

Àwọn ọ̀tá rẹ yóò ba búrúbúrú níwájú rẹ.+

 4 Gbogbo ayé yóò forí balẹ̀ fún ọ;+

Wọ́n á kọ orin ìyìn sí ọ,

Wọ́n á sì kọ orin ìyìn sí orúkọ rẹ.”+ (Sélà)

 5 Ẹ wá wo àwọn iṣẹ́ Ọlọ́run.

Àwọn ohun tó ṣe fún àwọn ọmọ èèyàn jẹ́ àgbàyanu.+

 6 Ó sọ òkun di ilẹ̀ gbígbẹ;+

Wọ́n fi ẹsẹ̀ la odò kọjá.+

Níbẹ̀, à ń yọ̀ nítorí ohun tó ṣe.+

 7 Ó ń fi agbára ńlá rẹ̀ ṣàkóso títí láé.+

Ojú rẹ̀ ń wo àwọn orílẹ̀-èdè.+

Kí àwọn alágídí má ṣe gbé ara wọn ga.+ (Sélà)

 8 Ẹ yin Ọlọ́run wa,+

Ẹ sì jẹ́ kí a gbọ́ ohùn ìyìn rẹ̀.

 9 Ó dá ẹ̀mí wa sí;*+

Kò jẹ́ kí a kọsẹ̀.*+

10 Ìwọ Ọlọ́run, o ti yẹ̀ wá wò;+

O ti yọ́ wa mọ́ bí ẹni yọ́ fàdákà mọ́.

11 O fi àwọ̀n rẹ mú wa;

O gbé ẹrù tó ń wọni lọ́rùn lé wa lórí.*

12 O jẹ́ kí ẹni kíkú máa gùn wá;*

A la iná àti omi kọjá;

Lẹ́yìn náà, o mú wa wá sí ibi tó tura.

13 Màá mú odindi ẹbọ sísun wá sí ilé rẹ;+

Màá san àwọn ẹ̀jẹ́ mi fún ọ+

14 Èyí tí ètè mi ṣèlérí,+

Tí ẹnu mi sì sọ nígbà tí mo wà nínú ìdààmú.

15 Màá fi àwọn ẹran àbọ́sanra rú ẹbọ sísun sí ọ

Pẹ̀lú èéfín àwọn àgbò tí a fi rúbọ.

Màá fi àwọn akọ màlúù pẹ̀lú àwọn òbúkọ rúbọ. (Sélà)

16 Ẹ wá gbọ́, gbogbo ẹ̀yin tó bẹ̀rù Ọlọ́run,

Màá sọ ohun tó ṣe fún mi.*+

17 Mo fi ẹnu mi ké pè é,

Mo sì fi ahọ́n mi yìn ín lógo.

18 Ká ní mo ti gbèrò ohun búburú lọ́kàn mi,

Jèhófà kò ní gbọ́ mi.+

19 Àmọ́, Ọlọ́run gbọ́;+

Ó fetí sí àdúrà mi.+

20 Ìyìn ni fún Ọlọ́run, ẹni tí kò kọ àdúrà mi,

Tí kò sì fawọ́ ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ sẹ́yìn lórí mi.

Sí olùdarí; kí a kọ ọ́ pẹ̀lú àwọn ohun ìkọrin olókùn tín-ín-rín. Orin atunilára. Orin.

67 Ọlọ́run yóò ṣojú rere sí wa, yóò sì bù kún wa;

Yóò mú kí ojú rẹ̀ tàn sí wa lára+ (Sélà)

 2 Kí àwọn èèyàn lè mọ ọ̀nà rẹ ní gbogbo ayé+

Àti àwọn iṣẹ́ ìgbàlà rẹ láàárín gbogbo orílẹ̀-èdè.+

 3 Kí àwọn èèyàn máa yìn ọ́, Ọlọ́run;

Kí gbogbo àwọn èèyàn máa yìn ọ́.

 4 Kí inú àwọn orílẹ̀-èdè máa dùn, kí wọ́n sì máa kígbe ayọ̀,+

Nítorí wàá ṣèdájọ́ àwọn èèyàn lọ́nà tó tọ́.+

Wàá ṣamọ̀nà àwọn orílẹ̀-èdè ayé. (Sélà)

 5 Kí àwọn èèyàn máa yìn ọ́, Ọlọ́run;

Kí gbogbo àwọn èèyàn máa yìn ọ́.

 6 Ilẹ̀ yóò mú èso jáde;+

Ọlọ́run, àní Ọlọ́run wa, yóò bù kún wa.+

 7 Ọlọ́run yóò bù kún wa,

Gbogbo ayé yóò sì máa bẹ̀rù rẹ̀.*+

Sí olùdarí. Ti Dáfídì. Orin atunilára. Orin.

68 Kí Ọlọ́run dìde, kí àwọn ọ̀tá rẹ̀ tú ká,

Kí àwọn tó kórìíra rẹ̀ sì sá kúrò níwájú rẹ̀.+

 2 Bí afẹ́fẹ́ ṣe ń gbá èéfín lọ, bẹ́ẹ̀ ni kí o gbá wọn lọ;

Bí ìda ṣe ń yọ́ níwájú iná,

Bẹ́ẹ̀ ni kí àwọn ẹni burúkú ṣègbé níwájú Ọlọ́run.+

 3 Àmọ́ jẹ́ kí inú àwọn olódodo máa dùn;+

Kí ayọ̀ wọn kún níwájú Ọlọ́run,

Kí ìdùnnú wọn sì ṣubú layọ̀.

 4 Ẹ kọrin sí Ọlọ́run; ẹ fi orin yin* orúkọ rẹ̀.+

Ẹ kọrin sí Ẹni tó ń la àwọn aṣálẹ̀ tó tẹ́jú* kọjá.

Jáà* ni orúkọ rẹ̀!+ Ẹ máa yọ̀ níwájú rẹ̀!

 5 Bàbá àwọn ọmọ aláìníbaba àti ẹni tó ń dáàbò bo* àwọn opó+

Ni Ọlọ́run nínú ibùgbé rẹ̀ mímọ́.+

 6 Ọlọ́run ń fún àwọn tó dá wà ní ilé tí wọ́n á máa gbé;+

Ó ń mú àwọn ẹlẹ́wọ̀n jáde wá sínú aásìkí.+

Àmọ́ ilẹ̀ gbígbẹ ni àwọn alágídí* yóò máa gbé.+

 7 Ọlọ́run, nígbà tí o darí* àwọn èèyàn rẹ,+

Nígbà tí o gba aṣálẹ̀ kọjá, (Sélà)

 8 Ayé mì tìtì;+

Ọ̀run rọ òjò* nítorí Ọlọ́run;

Sínáì yìí mì tìtì nítorí Ọlọ́run, àní Ọlọ́run Ísírẹ́lì.+

 9 O mú kí òjò rọ̀ lọ́pọ̀lọpọ̀, ìwọ Ọlọ́run;

O sọ agbára àwọn èèyàn* rẹ tí àárẹ̀ mú dọ̀tun.

10 Wọ́n gbé inú àwọn àgọ́ tó wà ní ibùdó rẹ;+

Ọlọ́run, nínú oore rẹ, o pèsè fún àwọn aláìní.

11 Jèhófà pa àṣẹ;

Àwọn obìnrin tó ń kéde ìhìn rere jẹ́ agbo ọmọ ogun ńlá.+

12 Àwọn ọba ẹgbẹ́ ọmọ ogun sá lọ,+ wọ́n fẹsẹ̀ fẹ!

Obìnrin tí kò kúrò nílé pín nínú ẹrù tí wọ́n kó bọ̀.+

13 Bí ẹ̀yin ọkùnrin tilẹ̀ dùbúlẹ̀ sáàárín iná ibùdó,*

Ẹ máa ní àdàbà tí a fi fàdákà bo ìyẹ́ apá rẹ̀,

Tí a sì fi wúrà tó dáa* bo ìyẹ́ tó fi ń fò.

14 Nígbà tí Olódùmarè tú àwọn ọba ilẹ̀ náà ká,+

Yìnyín bọ́ ní Sálímónì.*

15 Òkè Báṣánì+ jẹ́ òkè Ọlọ́run;*

Òkè Báṣánì jẹ́ òkè tó ní àwọn orí ṣóńṣó.

16 Ẹ̀yin òkè tó ní àwọn orí ṣóńṣó, kí ló dé tí ẹ̀ ń jowú

Òkè tí Ọlọ́run yàn* láti máa gbé inú rẹ̀?+

Dájúdájú, Jèhófà yóò máa gbé ibẹ̀ títí láé.+

17 Àwọn kẹ̀kẹ́ ogun Ọlọ́run jẹ́ ẹgbẹẹgbàárùn-ún, ẹgbẹẹgbẹ̀rún lọ́nà ẹgbẹẹgbẹ̀rún.+

Jèhófà wá láti Sínáì sínú ibi mímọ́.+

18 Ìwọ gòkè lọ sí ibi gíga;+

O kó àwọn èèyàn lẹ́rú;

O kó àwọn ẹ̀bùn tí ó jẹ́ èèyàn,+

Kódà, àwọn alágídí,+ láti máa gbé láàárín wọn, Jáà Ọlọ́run.

19 Ìyìn ni fún Jèhófà, tó ń bá wa gbé ẹrù wa lójoojúmọ́,+

Ọlọ́run tòótọ́, olùgbàlà wa. (Sélà)

20 Ọlọ́run tòótọ́ ni Ọlọ́run tó ń gbà wá là;+

Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sì ń gbani lọ́wọ́ ikú.+

21 Bẹ́ẹ̀ ni, Ọlọ́run yóò fọ́ orí àwọn ọ̀tá rẹ̀,

Ìyẹn àtàrí ẹnikẹ́ni tí kò jáwọ́* nínú ìwà ibi.+

22 Jèhófà sọ pé: “Màá mú wọn pa dà láti Báṣánì;+

Màá mú wọn pa dà látinú ibú òkun,

23 Kí o lè wẹ ẹsẹ̀ rẹ nínú ẹ̀jẹ̀+ àwọn ọ̀tá,

Kí ahọ́n àwọn ajá rẹ sì lè lá ẹ̀jẹ̀ wọn.”

24 Wọ́n rí ìkọ́wọ̀ọ́rìn rẹ, Ọlọ́run,

Ìkọ́wọ̀ọ́rìn Ọlọ́run mi, Ọba mi, sínú ibi mímọ́.+

25 Àwọn akọrin ń lọ níwájú, àwọn tó ń ta ohun ìkọrin olókùn tín-ín-rín ń tẹ̀ lé wọn,+

Àwọn ọ̀dọ́bìnrin tó ń lu ìlù tanboríìnì sì wà ní àárín.+

26 Ẹ yin Ọlọ́run láàárín ọ̀pọ̀ èèyàn tó pé jọ;*

Ẹ yin Jèhófà, ẹ̀yin tí ẹ wá láti Orísun Ísírẹ́lì.+

27 Ibẹ̀ ni Bẹ́ńjámínì,+ tó kéré jù lọ, ti ń ṣẹ́gun wọn,

Bákan náà ni àwọn olórí Júdà pẹ̀lú ọ̀pọ̀ èèyàn wọn tó ń pariwo

Àti àwọn olórí Sébúlúnì pẹ̀lú àwọn olórí Náfútálì.

28 Ọlọ́run rẹ ti pàṣẹ pé kí o lágbára.

Ìwọ Ọlọ́run, fi agbára rẹ hàn, o ti gbé ìgbésẹ̀ nítorí wa.+

29 Nítorí tẹ́ńpìlì rẹ tó wà ní Jerúsálẹ́mù,+

Àwọn ọba yóò mú àwọn ẹ̀bùn wá fún ọ.+

30 Bá ẹranko tó wà nínú àwọn esùsú* wí,

Àpéjọ àwọn akọ màlúù+ àti àwọn ọmọ màlúù,

Títí àwọn èèyàn á fi tẹrí ba tí wọ́n á sì mú fàdákà wá.*

Àmọ́, tú àwọn èèyàn tó fẹ́ràn ogun ká.

 31 A ó mú àwọn ohun tí a fi idẹ ṣe* wá láti Íjíbítì;+

Kúṣì yóò yára mú àwọn ẹ̀bùn wá fún Ọlọ́run.

32 Ẹ̀yin ìjọba ayé, ẹ kọrin sí Ọlọ́run,+

Ẹ fi orin yin* Jèhófà, (Sélà)

 33 Ẹni tó ń gun ọ̀run àwọn ọ̀run tó ti wà láti ayébáyé.+

Wò ó! Ó fi ohùn rẹ̀ sán ààrá, ohùn rẹ̀ alágbára ńlá.

34 Ti Ọlọ́run ni agbára.+

Ọlá ńlá rẹ̀ wà lórí Ísírẹ́lì

Àti okun rẹ̀ lójú ọ̀run.*

35 Ọlọ́run yẹ lẹ́ni tí à ń bẹ̀rù ní ibi mímọ́ rẹ̀* títóbi lọ́lá.+

Òun ni Ọlọ́run Ísírẹ́lì,

Ẹni tó ń fún àwọn èèyàn ní okun àti agbára.+

Ẹ yin Ọlọ́run.

Sí olùdarí; kí a yí i sí “Òdòdó Lílì.” Ti Dáfídì.

69 Gbà mí là, Ọlọ́run, torí pé omi ti fẹ́ gba ẹ̀mí mi.*+

 2 Mo ti rì sínú ẹrẹ̀ tó jìn, níbi tí kò sí ilẹ̀ tó ṣeé dúró lé.+

Mo ti dé inú ibú omi,

Odò tó ń yára ṣàn sì gbé mi lọ.+

 3 Ó ti rẹ̀ mí nítorí igbe tí mò ń ké;+

Ọ̀fun mi ti há.

Ojú mi ti di bàìbàì bí mo ṣe ń dúró de Ọlọ́run mi.+

 4 Àwọn tó kórìíra mi láìnídìí+

Pọ̀ ju irun orí mi lọ.

Àwọn tó fẹ́ pa mí,

Àwọn oníbékebèke tí wọ́n jẹ́ ọ̀tá mi* ti pọ̀ gan-an.

Àwọn nǹkan tí mi ò jí ni wọ́n ní kí n dá pa dà tipátipá.

 5 Ọlọ́run, o mọ ìwà òmùgọ̀ mi,

Ẹ̀bi mi kò sì pa mọ́ lójú rẹ.

 6 Kí àwọn tó gbẹ́kẹ̀ lé ọ má ṣe rí ìtìjú nítorí tèmi,

Olúwa Ọba Aláṣẹ, Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun.

Kí àwọn tó ń wá ọ má ṣe tẹ́ nítorí tèmi,

Ìwọ Ọlọ́run Ísírẹ́lì.

 7 Wọ́n pẹ̀gàn mi nítorí rẹ;+

Ẹ̀tẹ́ bá mi.+

 8 Mo ti di àlejò sí àwọn arákùnrin mi,

Mo sì ti di àjèjì sí àwọn ọmọ ìyá mi.+

 9 Ìtara ilé rẹ ti gbà mí lọ́kàn,+

Ẹ̀gàn ẹnu àwọn tó ń pẹ̀gàn rẹ sì ti wá sórí mi.+

10 Nígbà tí mo rẹ ara* mi sílẹ̀ pẹ̀lú ààwẹ̀ gbígbà,*

Wọ́n pẹ̀gàn mi nítorí èyí.

11 Nígbà tí mo gbé aṣọ ọ̀fọ̀* wọ̀,

Mo di ẹni ẹ̀gàn* lójú wọn.

12 Èmi ni àwọn tó ń jókòó ní ẹnubodè fi ń ṣe ọ̀rọ̀ sọ,

Ọ̀rọ̀ mi sì ni àwọn ọ̀mùtí fi ń ṣe orin kọ.

13 Àmọ́, kí àdúrà mi wá sọ́dọ̀ rẹ,

Jèhófà, ní àkókò ìtẹ́wọ́gbà.+

Nínú ọ̀pọ̀ ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀, ìwọ Ọlọ́run,

Fi àwọn iṣẹ́ ìgbàlà rẹ dá mi lóhùn.+

14 Yọ mí nínú ẹrẹ̀;

Má ṣe jẹ́ kí n rì.

Gbà mí lọ́wọ́ àwọn tó kórìíra mi

Kí o sì yọ mí nínú ibú omi.+

15 Má ṣe jẹ́ kí omi tó ń yára ṣàn gbé mi lọ,+

Tàbí kí ibú omi bò mí mọ́lẹ̀,

Tàbí kí kànga* pa dé mọ́ mi.+

16 Dá mi lóhùn, Jèhófà, nítorí ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ dára.+

Nínú ọ̀pọ̀ àánú rẹ, yíjú sí mi,+

17 Má sì fi ojú rẹ pa mọ́ fún ìránṣẹ́ rẹ.+

Tètè dá mi lóhùn, nítorí mo wà nínú wàhálà.+

18 Sún mọ́ mi, kí o sì gbà mí sílẹ̀;*

Gbà mí lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá mi.

19 O mọ ẹ̀gàn, ìtìjú àti ẹ̀tẹ́ tó bá mi.+

O rí gbogbo àwọn ọ̀tá mi.

20 Ẹ̀gàn ti dá ọgbẹ́ sí mi lọ́kàn, ọgbẹ́ náà kò sì ṣeé wò sàn.*

Mò ń retí pé màá rí ẹni bá mi kẹ́dùn, àmọ́ kò sí,+

Mo sì ń retí pé màá rí olùtùnú, àmọ́ mi ò rí ìkankan.+

21 Májèlé* ni wọ́n fún mi dípò oúnjẹ,+

Ọtí kíkan ni wọ́n sì fún mi láti fi pa òùngbẹ.+

22 Jẹ́ kí tábìlì wọn di pańpẹ́ fún wọn,

Kí aásìkí wọn sì di ìdẹkùn.+

23 Jẹ́ kí ojú wọn ṣú, kí wọ́n má lè ríran,

Sì mú kí ẹsẹ̀* wọn máa gbọ̀n nígbà gbogbo.

24 Da ìbínú* rẹ sí wọn lórí,

Sì mú kí ìbínú rẹ tó ń jó bí iná dé bá wọn.+

25 Jẹ́ kí ibùdó wọn* di ahoro;

Kí ó má ṣe sí ẹnì kankan tí á máa gbé inú àgọ́ wọn.+

26 Nítorí ẹni tí o ti lù ni wọ́n ń lépa,

Wọ́n sì ń sọ nípa ìrora àwọn tí o ṣe léṣe.

27 Jẹ́ kí wọ́n jẹ ẹ̀bi lé ẹ̀bi,

Kí wọ́n má sì ní ìpín kankan nínú òdodo rẹ.

28 Jẹ́ kí a pa orúkọ wọn rẹ́ kúrò nínú ìwé àwọn alààyè,*+

Kí a má sì kọ orúkọ wọn mọ́ àwọn olódodo.+

29 Ní tèmi, ìyà ń jẹ mí, mo sì wà nínú ìrora.+

Ìwọ Ọlọ́run, kí agbára rẹ tó ń gbani là dáàbò bò mí.

30 Màá kọ orin ìyìn sí orúkọ Ọlọ́run,

Màá sì fi ọpẹ́ gbé e ga.

31 Èyí máa mú inú Jèhófà dùn ju akọ màlúù,

Ju akọ ọmọ màlúù tó ní ìwo àti pátákò.+

32 Àwọn oníwà pẹ̀lẹ́ yóò rí i, wọ́n á sì yọ̀.

Ẹ̀yin tí ẹ̀ ń wá Ọlọ́run, kí ọkàn yín sọ jí.

33 Nítorí Jèhófà ń fetí sí àwọn aláìní,+

Kò sì ní fojú pa àwọn èèyàn rẹ̀ tó wà lóko ẹrú rẹ́.+

34 Kí ọ̀run àti ayé máa yìn ín,+

Àwọn òkun àti ohun gbogbo tó ń rìn nínú wọn.

35 Ọlọ́run yóò gba Síónì là,+

Yóò tún àwọn ìlú Júdà kọ́,

Wọ́n á máa gbé ibẹ̀, àwọn ni yóò sì ni ín.*

36 Àtọmọdọ́mọ àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ yóò jogún rẹ̀,+

Àwọn tó fẹ́ràn orúkọ rẹ̀ + yóò sì máa gbé inú rẹ̀.

Sí olùdarí. Ti Dáfídì, kí ó jẹ́ ìránnilétí.*

70 Ọlọ́run, gbà mí;

Jèhófà, tètè wá ràn mí lọ́wọ́.+

 2 Kí ìtìjú àti ẹ̀tẹ́ bá

Àwọn tó fẹ́ gba ẹ̀mí* mi.

Kí àwọn tí inú wọn ń dùn sí àjálù tó bá mi

Sá pa dà nínú ẹ̀tẹ́.

 3 Kí àwọn tó ń sọ pé: “Àháà! Àháà!”

Fi ìtìjú sá pa dà.

 4 Àmọ́ kí àwọn tó ń wá ọ

Máa yọ̀, kí inú wọn sì máa dùn nítorí rẹ.+

Kí àwọn tó nífẹ̀ẹ́ àwọn iṣẹ́ ìgbàlà rẹ máa sọ nígbà gbogbo pé:

“Ẹ gbé Ọlọ́run ga!”

 5 Àmọ́, aláìní ni mí, mi ò sì ní olùrànlọ́wọ́;+

Ọlọ́run, tètè wá ràn mí lọ́wọ́.+

Ìwọ ni olùrànlọ́wọ́ mi àti olùgbàlà mi;+

Jèhófà, má ṣe jẹ́ kó pẹ́.+

71 Jèhófà, ìwọ ni mo fi ṣe ibi ààbò.

Má ṣe jẹ́ kí ojú tì mí láé.+

 2 Gbà mí sílẹ̀, kí o sì gbà mí là nínú òdodo rẹ.

Tẹ́tí sí mi,* kí o sì gbà mí sílẹ̀.+

 3 Di àpáta ààbò fún mi

Kí n lè máa ríbi wọ̀ nígbà gbogbo.

Pàṣẹ láti gbà mí là,

Nítorí ìwọ ni àpáta mi àti ibi ààbò mi.+

 4 Ọlọ́run mi, gbà mí lọ́wọ́ ẹni burúkú,+

Gbà mí lọ́wọ́ àwọn tó ń ni èèyàn lára láìtọ́.

 5 Nítorí ìwọ ni ìrètí mi, Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ;

Ìwọ ni mo gbẹ́kẹ̀ lé* láti ìgbà èwe mi wá.+

 6 Ìwọ ni mo gbára lé láti ìgbà tí wọ́n ti bí mi;

Ìwọ ló gbé mi jáde látinú ìyá mi.+

Gbogbo ìgbà ni mò ń yìn ọ́.

 7 Mo dà bí iṣẹ́ ìyanu lójú ọ̀pọ̀ èèyàn,

Àmọ́ ìwọ ni ibi ààbò mi tó lágbára.

 8 Ìyìn rẹ kún ẹnu mi;+

Mò ń sọ nípa ọlá ńlá rẹ láti àárọ̀ ṣúlẹ̀.

 9 Má ṣe gbé mi sọ nù ní ọjọ́ ogbó mi;+

Má pa mí tì nígbà tí mi ò bá lágbára mọ́.+

10 Àwọn ọ̀tá mi ń sọ̀rọ̀ tí kò dáa sí mi,

Àwọn tó sì fẹ́ gba ẹ̀mí* mi gbìmọ̀ pọ̀,+

11 Wọ́n ń sọ pé: “Ọlọ́run ti pa á tì.

Ẹ lé e, kí ẹ sì mú un, torí kò sẹ́ni tó máa gbà á sílẹ̀.”+

12 Ọlọ́run, má jìnnà sí mi.

Ìwọ Ọlọ́run mi, tètè wá ràn mí lọ́wọ́.+

13 Kí ojú ti àwọn tó ń ta kò mí,*

Kí wọ́n sì ṣègbé.+

Ní ti àwọn tó ń wá àjálù mi,

Kí ìtìjú àti ẹ̀tẹ́ bò wọ́n mọ́lẹ̀.+

14 Àmọ́ ní tèmi, èmi yóò máa dúró dè ọ́;

Màá fi kún ìyìn rẹ.

15 Ẹnu mi yóò máa ròyìn òdodo rẹ+

Àti àwọn iṣẹ́ ìgbàlà rẹ láti àárọ̀ ṣúlẹ̀,

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n pọ̀ ju ohun tí mo lè lóye* lọ.+

16 Màá wá sọ nípa àwọn iṣẹ́ ńlá rẹ,

Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ;

Màá mẹ́nu kan òdodo rẹ, tìrẹ nìkan.

17 Ọlọ́run, o ti kọ́ mi láti ìgbà èwe mi wá,+

Títí di báyìí, mò ń kéde àwọn iṣẹ́ àgbàyanu rẹ.+

18 Kódà tí mo bá darúgbó, tí mo sì hu ewú, Ọlọ́run, má fi mí sílẹ̀.+

Jẹ́ kí n lè sọ nípa agbára* rẹ fún ìran tó ń bọ̀,

Kí n sì sọ nípa agbára ńlá rẹ fún gbogbo àwọn tó ń bọ̀.+

19 Ọlọ́run, òdodo rẹ ga dé òkè;+

O ti ṣe àwọn ohun ńlá;

Ọlọ́run, ta ló dà bí rẹ?+

20 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé o ti mú kí n rí ọ̀pọ̀ wàhálà àti àjálù,+

Mú kí n sọ jí lẹ́ẹ̀kan sí i;

Gbé mi dìde láti inú kòtò* ilẹ̀ ayé.+

21 Jẹ́ kí ọlá mi pọ̀ sí i,

Rọ̀gbà yí mi ká, kí o sì tù mí nínú.

22 Nígbà náà, màá fi ohun ìkọrin olókùn tín-ín-rín yìn ọ́

Nítorí òtítọ́ rẹ, Ọlọ́run mi.+

Màá fi háàpù kọ orin ìyìn sí ọ,*

Ìwọ Ẹni Mímọ́ Ísírẹ́lì.

23 Ètè mi yóò máa kígbe ayọ̀ bí mo ṣe ń kọ orin ìyìn sí ọ,+

Nítorí o gba ẹ̀mí mi là.*+

24 Ahọ́n mi yóò máa sọ nípa* òdodo rẹ láti àárọ̀ ṣúlẹ̀,+

Ojú yóò ti àwọn tó ń wá ìparun mi, wọ́n á sì tẹ́.+

Nípa Sólómọ́nì.

72 Ọlọ́run, sọ àwọn ìdájọ́ rẹ fún ọba,

Kí o sì kọ́ ọmọ ọba ní òdodo rẹ.+

 2 Kí ó fi òdodo gba ẹjọ́ àwọn èèyàn rẹ rò,

Kí ó sì ṣe ìdájọ́ òdodo fún àwọn aláìní.+

 3 Kí àwọn òkè ńlá fún àwọn èèyàn ní àlàáfíà,

Kí àwọn òkè kéékèèké sì mú òdodo wá.

 4 Kí ó gbèjà* àwọn tó jẹ́ aláìní,

Kí ó gba àwọn ọmọ òtòṣì là,

Kí ó sì tẹ àwọn oníjìbìtì rẹ́.+

 5 Láti ìran dé ìran,

Wọ́n á máa bẹ̀rù rẹ níwọ̀n ìgbà tí oòrùn bá ṣì wà,

Tí òṣùpá sì ń yọ.+

 6 Yóò dà bí òjò tó ń rọ̀ sórí koríko tí a gé,

Bí ọ̀wààrà òjò tó ń mú kí ilẹ̀ rin.+

 7 Ní àkókò rẹ̀, àwọn olódodo yóò gbilẹ̀,*+

Àlàáfíà yóò sì gbilẹ̀+ títí òṣùpá kò fi ní sí mọ́.

 8 Yóò ní àwọn ọmọ abẹ́* láti òkun dé òkun

Àti láti Odò* dé àwọn ìkángun ayé.+

 9 Àwọn tó ń gbé ní aṣálẹ̀ yóò tẹrí ba níwájú rẹ̀,

Àwọn ọ̀tá rẹ̀ yóò sì lá erùpẹ̀.+

10 Àwọn ọba Táṣíṣì àti ti àwọn erékùṣù yóò máa san ìṣákọ́lẹ̀.*+

Àwọn ọba Ṣébà àti ti Sébà yóò mú ẹ̀bùn wá.+

11 Gbogbo àwọn ọba yóò tẹrí ba níwájú rẹ̀,

Gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè yóò sì máa sìn ín.

12 Nítorí yóò gba àwọn aláìní tó ń kígbe fún ìrànlọ́wọ́ sílẹ̀,

Yóò sì gba tálákà àti ẹni tí kò ní olùrànlọ́wọ́.

13 Yóò ṣàánú aláìní àti tálákà,

Yóò sì gba ẹ̀mí* àwọn tálákà là.

14 Yóò gbà wọ́n* lọ́wọ́ ìnira àti ìwà ipá,

Ẹ̀jẹ̀ wọn yóò sì ṣe iyebíye lójú rẹ̀.

15 Kí ó máa wà láàyè, kí a sì fún un ní wúrà Ṣébà.+

Kí a máa gbàdúrà fún un nígbà gbogbo,

Kí a sì máa bù kún un láti àárọ̀ ṣúlẹ̀.

16 Ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ oúnjẹ* máa wà lórí ilẹ̀;+

Ó máa kún àkúnwọ́sílẹ̀ lórí àwọn òkè.

Èso rẹ̀ máa dára bíi ti Lẹ́bánónì,+

Nínú àwọn ìlú, àwọn èèyàn máa pọ̀ bí ewéko ilẹ̀.+

17 Kí orúkọ rẹ̀ wà títí láé,+

Kí ó sì máa lókìkí níwọ̀n ìgbà tí oòrùn bá ṣì wà.

Kí àwọn èèyàn gba ìbùkún fún ara wọn nípasẹ̀ rẹ̀;+

Kí gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè pè é ní aláyọ̀.

18 Ìyìn ni fún Jèhófà Ọlọ́run, Ọlọ́run Ísírẹ́lì,+

Òun nìkan ló ń ṣe àwọn ohun àgbàyanu.+

19 Kí á yin orúkọ rẹ̀ ológo títí láé,+

Kí ògo rẹ̀ sì kún gbogbo ayé.+

Àmín àti Àmín.

20 Ibí ni àdúrà Dáfídì, ọmọ Jésè+ parí sí.

ÌWÉ KẸTA

(Sáàmù 73-89)

Orin Ásáfù.+

73 Ní tòótọ́, Ọlọ́run ṣe rere fún Ísírẹ́lì, fún àwọn tí ọkàn wọn mọ́.+

 2 Ní tèmi, ẹsẹ̀ mi fẹ́rẹ̀ẹ́ yà kúrò lójú ọ̀nà;

Díẹ̀ ló kù kí ẹsẹ̀ mi yọ̀ tẹ̀rẹ́.+

 3 Nítorí mo jowú àwọn agbéraga*

Nígbà tí mo rí àlàáfíà àwọn ẹni burúkú.+

 4 Ikú wọn kì í mú ìrora lọ́wọ́;

Ara wọn jí pépé.*+

 5 Ìdààmú tó ń bá àwọn èèyàn yòókù kì í bá wọn,+

Ìyà tó sì ń jẹ àwọn èèyàn tó kù kì í jẹ wọ́n.+

 6 Nítorí náà, ìgbéraga ni ìlẹ̀kẹ̀ ọrùn wọn;+

Wọ́n gbé ìwà ipá wọ̀ bí aṣọ.

 7 Aásìkí* wọn mú kí ẹ̀rẹ̀kẹ́ wọn yọ;

Wọ́n ti ní kọjá ohun tí ọkàn wọn rò.

 8 Wọ́n ń fini ṣẹ̀sín, wọ́n sì ń sọ ohun tó burú.+

Wọ́n ń fi ìgbéraga halẹ̀ mọ́ àwọn èèyàn láti ni wọ́n lára.+

 9 Wọ́n ń sọ̀rọ̀ bíi pé wọ́n ga dé ọ̀run,

Ahọ́n wọn sì ń sọ̀rọ̀ ìgbéraga káàkiri ayé.

10 Nítorí náà, àwọn èèyàn rẹ̀* yíjú sọ́dọ̀ wọn,

Wọ́n sì mu nínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ omi wọn.

11 Wọ́n ń sọ pé: “Báwo ni Ọlọ́run ṣe fẹ́ mọ̀?+

Ṣé Ẹni Gíga Jù Lọ mọ ohun tó ń ṣẹlẹ̀ ni?”

12 Bí ọ̀rọ̀ àwọn ẹni burúkú ṣe rí nìyí, àwọn tí gbogbo nǹkan dẹrùn fún.+

Wọ́n ń kó ọrọ̀ jọ ṣáá.+

13 Ó dájú pé lásán ni mo pa ọkàn mi mọ́,

Tí mo sì wẹ ọwọ́ mi mọ́ pé mo jẹ́ aláìmọwọ́mẹsẹ̀.+

14 Ìdààmú bá mi láti àárọ̀ ṣúlẹ̀;+

Àràárọ̀ ni mò ń gba ìbáwí.+

15 Ká ní mo ti sọ irú ọ̀rọ̀ yìí ni,

Mi ò bá ti dalẹ̀ àwọn èèyàn* rẹ.

16 Nígbà tí mo sapá láti lóye rẹ̀,

Ó dà mí láàmú

17 Títí mo fi wọ ibi mímọ́ títóbi lọ́lá ti Ọlọ́run,

Tí mo sì wá mọ ọjọ́ ọ̀la wọn.

18 Ó dájú pé orí ilẹ̀ tó ń yọ̀ lo gbé wọn lé.+

Kí wọ́n lè ṣubú kí wọ́n sì pa run.+

19 Ẹ wo bí wọ́n ti pa rẹ́ lójijì!+

Ẹ wo bí òpin ṣe dé bá wọn lójijì, tí wọ́n sì pa run!

20 Jèhófà, ńṣe ló dà bí àlá nígbà téèyàn bá jí,

Nígbà tí o bá dìde, wàá gbé wọn kúrò lọ́kàn.*

21 Àmọ́ ọkàn mi korò,+

Inú mi lọ́hùn-ún* sì ń ro mí gógó.

22 Mi ò nírònú, mi ò sì lóye;

Mo dà bí ẹranko tí kò ní làákàyè níwájú rẹ.

23 Àmọ́ ní báyìí, ọ̀dọ̀ rẹ ni mo wà nígbà gbogbo;

O ti di ọwọ́ ọ̀tún mi mú.+

24 O fi ìmọ̀ràn rẹ ṣamọ̀nà mi,+

Lẹ́yìn náà, wàá mú mi wọnú ògo.+

25 Ta ni mo ní lọ́run?

Lẹ́yìn rẹ, kò sí ohun míì tó wù mí ní ayé.+

26 Àárẹ̀ lè mú ara mi àti ọkàn mi,

Àmọ́ Ọlọ́run ni àpáta ọkàn mi àti ìpín mi títí láé.+

27 Ní tòótọ́, àwọn tó jìnnà sí ọ yóò ṣègbé.

Gbogbo àwọn tó fi ọ́ sílẹ̀ lọ ṣe ìṣekúṣe* ni wàá pa run.*+

28 Àmọ́ ní tèmi, sísúnmọ́ Ọlọ́run dára fún mi.+

Mo ti fi Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ ṣe ibi ààbò mi,

Kí n lè máa kéde gbogbo iṣẹ́ rẹ.+

Másíkílì.* Ti Ásáfù.+

74 Ọlọ́run, kí ló dé tí o fi kọ̀ wá sílẹ̀ títí láé?+

Kí nìdí tí ìbínú rẹ fi ń jó bí iná* lórí agbo ẹran tó wà ní ibi ìjẹko rẹ?+

 2 Rántí àwọn èèyàn* tí o ti yàn tipẹ́tipẹ́,+

Ẹ̀yà tí o rà pa dà láti fi ṣe ogún rẹ.+

Rántí Òkè Síónì, ibi tí o gbé.+

 3 Lọ sí àwọn ibi tó fìgbà gbogbo jẹ́ àwókù.+

Ọ̀tá ti ba gbogbo ohun tó wà ní ibi mímọ́ jẹ́.+

 4 Àwọn ọ̀tá rẹ ń bú ramúramù nínú ibi ìpàdé* rẹ.+

Wọ́n fi àwọn ọ̀págun wọn ṣe àmì síbẹ̀.

 5 Wọ́n dà bí àwọn ọkùnrin tó ń fi àáké dá igbó kìjikìji lu.

 6 Wọ́n fi àáké àti àwọn ọ̀pá onírin fọ́ àwọn iṣẹ́ ọnà ara rẹ̀.+

 7 Wọ́n sọ iná sí ibi mímọ́ rẹ.+

Wọ́n sọ àgọ́ ìjọsìn tí o fi orúkọ rẹ pè di aláìmọ́, wọ́n sì wó o lulẹ̀.

 8 Àwọn àti àwọn ọmọ wọn sọ nínú ọkàn wọn pé:

“Gbogbo ibi ìpàdé tó jẹ́ ti Ọlọ́run* ní ilẹ̀ náà la máa dáná sun.”

 9 Kò sí àmì kankan tí a rí;

Kò sí wòlíì kankan mọ́,

Kò sì sí ẹnì kankan nínú wa tó mọ bí èyí ṣe máa pẹ́ tó.

10 Ọlọ́run, ìgbà wo ni elénìní máa pẹ̀gàn rẹ dà?+

Ṣé ọ̀tá yóò máa hùwà àìlọ́wọ̀ sí orúkọ rẹ títí láé ni?+

11 Kí ló dé tí o fi fa ọwọ́ rẹ sẹ́yìn, ọwọ́ ọ̀tún rẹ?+

Nà án jáde láti àyà rẹ,* kí o sì pa wọ́n run.

12 Àmọ́, Ọlọ́run ni Ọba mi láti ayébáyé,

Ẹni tó ń ṣe àwọn iṣẹ́ ìgbàlà ní ayé.+

13 O fi agbára rẹ ru òkun sókè;+

O fọ́ orí àwọn ẹran ńlá inú òkun.

14 O fọ́ orí Léfíátánì;*

O fi ṣe oúnjẹ fún àwọn èèyàn, fún àwọn tó ń gbé aṣálẹ̀.

15 O la ọ̀nà fún àwọn ìsun omi àti odò;+

O mú kí àwọn odò tó ń ṣàn nígbà gbogbo gbẹ táútáú.+

16 Tìrẹ ni ọ̀sán, tìrẹ sì ni òru.

Ìwọ lo ṣe ìmọ́lẹ̀* àti oòrùn.+

17 O pa ààlà sí gbogbo ayé;+

O ṣe ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn àti ìgbà òtútù.+

18 Jèhófà, rántí bí ọ̀tá ṣe pẹ̀gàn rẹ,

Bí àwọn òmùgọ̀ ṣe hùwà àìlọ́wọ̀ sí orúkọ rẹ.+

19 Má ṣe fi ẹ̀mí* oriri rẹ fún àwọn ẹranko.

Ní ti ẹ̀mí àwọn èèyàn rẹ tí ìyà ń jẹ, má ṣe gbàgbé rẹ̀ títí láé.

20 Rántí májẹ̀mú tí o bá wa dá,

Nítorí pé àwọn ibi tó ṣókùnkùn ní ayé ti di ibùgbé àwọn oníwà ipá.

21 Kí ẹni tí a ni lára má ṣe yíjú pa dà nítorí ìjákulẹ̀;+

Kí aláìní àti tálákà máa yin orúkọ rẹ.+

22 Dìde, Ọlọ́run, gba ẹjọ́ ara rẹ rò.

Rántí bí àwọn òmùgọ̀ ṣe ń pẹ̀gàn rẹ láti àárọ̀ ṣúlẹ̀.+

23 Má gbàgbé ohun tí àwọn ọ̀tá rẹ ń sọ.

Ariwo àwọn tó ń pè ọ́ níjà ń lọ sókè nígbà gbogbo.

Sí olùdarí. Kí a yí i sí orin “Má Ṣe Pa Á Run.” Ti Ásáfù.+ Orin.

75 A fi ọpẹ́ fún ọ, Ọlọ́run, a fi ọpẹ́ fún ọ;

Orúkọ rẹ wà nítòsí,+

Àwọn èèyàn sì ń kéde àwọn iṣẹ́ àgbàyanu rẹ.

 2 O sọ pé: “Tí mo bá dá àkókò kan,

Màá ṣe ìdájọ́ bó ṣe tọ́.

 3 Nígbà tí ayé àti gbogbo àwọn tó ń gbé inú rẹ̀ yọ́,

Èmi ni kò jẹ́ kí àwọn òpó rẹ̀ yẹ̀.” (Sélà)

 4 Mo sọ fún àwọn tó ń fọ́nnu pé, “Ẹ má ṣe fọ́nnu,”

Mo sì sọ fún àwọn ẹni burúkú pé, “Ẹ má ṣe gbéra ga nítorí agbára* yín.

 5 Ẹ má ṣe gbé ara yín ga sókè nítorí agbára* yín

Tàbí kí ẹ fi ìgbéraga sọ̀rọ̀.

 6 Nítorí pé kì í ṣe

Ìlà oòrùn tàbí ìwọ̀ oòrùn tàbí gúúsù ni ìgbéga ti ń wá.

 7 Nítorí Ọlọ́run jẹ́ onídàájọ́.+

Á rẹ ẹnì kan wálẹ̀, á sì gbé ẹlòmíì ga.+

 8 Ife kan wà ní ọwọ́ Jèhófà;+

Wáìnì inú rẹ̀ ń ru, wọ́n sì pò ó pọ̀ dáadáa.

Ó dájú pé yóò dà á jáde,

Gbogbo àwọn ẹni burúkú ayé yóò mu ún tòun ti gẹ̀dẹ̀gẹ́dẹ̀ rẹ̀.”+

 9 Àmọ́ ní tèmi, màá kéde rẹ̀ títí láé;

Màá fi orin yin* Ọlọ́run Jékọ́bù.

10 Torí ó sọ pé: “Màá mú gbogbo agbára* ẹni burúkú kúrò,

Àmọ́ agbára* olódodo yóò pọ̀ sí i.”

Sí olùdarí; kí a kọ ọ́ pẹ̀lú àwọn ohun ìkọrin olókùn tín-ín-rín.+ Orin Ásáfù. Orin.

76 A mọ Ọlọ́run ní Júdà;+

Orúkọ rẹ̀ tóbi ní Ísírẹ́lì.+

 2 Àgọ́ rẹ̀ wà ní Sálẹ́mù,+

Ibùgbé rẹ̀ sì wà ní Síónì.+

 3 Ibẹ̀ ló ti ṣẹ́ àwọn ọfà oníná tó jáde látinú ọrun,

Títí kan apata àti idà pẹ̀lú àwọn nǹkan ìjà ogun míì.+ (Sélà)

 4 Ìwọ ń tàn yanran;*

O ní ọlá ńlá ju àwọn òkè tó ní àwọn ẹran.

 5 Wọ́n ti kó ẹrù àwọn tó nígboyà.

Oorun ti gbé wọn lọ;+

Gbogbo àwọn jagunjagun ò lè ṣe nǹkan kan.+

 6 Ọlọ́run Jékọ́bù, nípa ìbáwí rẹ,

Ẹṣin àti ẹni tó gun kẹ̀kẹ́ ẹṣin ti sùn lọ fọnfọn.+

 7 Ìwọ nìkan ló yẹ lẹ́ni tí à ń bẹ̀rù.+

Ta ló lè dúró níwájú ìbínú gbígbóná rẹ?+

 8 O kéde ìdájọ́ láti ọ̀run;+

Ẹ̀rù ba ayé, ó sì dákẹ́+

 9 Nígbà tí Ọlọ́run dìde láti mú ìdájọ́ ṣẹ,

Láti gba gbogbo àwọn oníwà pẹ̀lẹ́ ayé là.+ (Sélà)

10 Nítorí pé ìrunú èèyàn yóò yọrí sí ìyìn rẹ;+

Èyí tó kù lára ìrunú wọn ni ìwọ yóò fi ṣe ara rẹ lọ́ṣọ̀ọ́.

11 Ẹ jẹ́jẹ̀ẹ́ fún Jèhófà Ọlọ́run yín, kí ẹ sì san án,+

Kí gbogbo àwọn tó wà lọ́dọ̀ rẹ̀ mú ẹ̀bùn wọn wá pẹ̀lú ìbẹ̀rù.+

12 Yóò rẹ ògo* àwọn aṣáájú wálẹ̀;

Ó ń mú kí ẹ̀rù ba àwọn ọba ayé.

Sí olùdarí; lórí Jédútúnì.*+ Ti Ásáfù. Orin.

77 Màá fi ohùn mi ké pe Ọlọ́run;

Màá ké pe Ọlọ́run, yóò sì gbọ́ mi.+

 2 Ní ọjọ́ wàhálà mi, mo wá Jèhófà.+

Ní òru, mi ò dẹ́kun* títẹ́wọ́ àdúrà sí i.

Síbẹ̀, mi* ò gba ìtùnú.

 3 Nígbà tí mo rántí Ọlọ́run, mo kérora;+

Ìdààmú bá mi, mi ò sì lágbára mọ́.*+ (Sélà)

 4 Ìwọ mú kí ojú mi là sílẹ̀;

Wàhálà bá mi, mi ò sì lè sọ̀rọ̀.

 5 Mo rántí ìgbà àtijọ́,+

Àwọn ọdún tó ti kọjá tipẹ́tipẹ́.

 6 Ní òru, mo rántí orin mi;*+

Mo ṣàṣàrò nínú ọkàn mi;+

Mo* fara balẹ̀ ṣèwádìí.

 7 Ṣé títí láé ni Jèhófà máa ta wá nù ni?+

Ṣé kò ní ṣojú rere sí wa mọ́ láé ni?+

 8 Ṣé ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ ti dáwọ́ dúró títí ayé ni?

Ṣé ìlérí rẹ̀ máa já sí asán fún gbogbo ìran ni?

 9 Ṣé Ọlọ́run ti gbàgbé láti ṣojú rere ni,+

Àbí, ṣé ìbínú rẹ̀ ti dínà àánú rẹ̀ ni? (Sélà)

10 Ṣé ó yẹ kí n máa sọ ní gbogbo ìgbà pé: “Ohun tó ń kó ìdààmú bá* mi ni pé:+

Ẹni Gíga Jù Lọ ti kọ ẹ̀yìn* sí wa”?

11 Màá rántí àwọn iṣẹ́ Jáà;

Màá rántí àwọn iṣẹ́ àgbàyanu tí o ti ṣe tipẹ́tipẹ́.

12 Màá ṣe àṣàrò lórí gbogbo iṣẹ́ rẹ,

Màá sì ronú jinlẹ̀ nípa àwọn ohun tí o ṣe.+

13 Ọlọ́run, àwọn ọ̀nà rẹ jẹ́ mímọ́.

Ìwọ Ọlọ́run, ọlọ́run wo ló tóbi bí rẹ?+

14 Ìwọ ni Ọlọ́run tòótọ́, tó ń ṣe àwọn ohun àgbàyanu.+

O ti fi agbára rẹ han àwọn èèyàn.+

15 O fi agbára* rẹ gba àwọn èèyàn rẹ sílẹ̀,*+

Àwọn ọmọ Jékọ́bù àti ti Jósẹ́fù. (Sélà)

16 Omi rí ọ, ìwọ Ọlọ́run;

Omi rí ọ, ó sì dà rú.+

Ibú omi ru gùdù.

17 Àwọsánmà da omi sílẹ̀.

Ojú ọ̀run tó ṣú dẹ̀dẹ̀ sán ààrá,

Àwọn ọfà rẹ sì ń fò síbí sọ́hùn-ún.+

18 Ìró ààrá rẹ+ dà bí ìró àgbá kẹ̀kẹ́ ẹṣin;

Mànàmáná tó ń kọ mú kí ilẹ̀ ayé tí à ń gbé* mọ́lẹ̀;+

Ayé mì tìtì, ó sì mì jìgìjìgì.+

19 Ọ̀nà rẹ gba inú òkun kọjá,+

Ipa ọ̀nà rẹ sì gba inú omi púpọ̀ kọjá;

Àmọ́ a kò lè rí ipa ẹsẹ̀ rẹ.

20 O darí àwọn èèyàn rẹ bí agbo ẹran,+

Lábẹ́ àbójútó* Mósè àti Áárónì.+

Másíkílì.* Ti Ásáfù.+

78 Ẹ fetí sí òfin* mi, ẹ̀yin èèyàn mi;

Ẹ tẹ́tí sí àwọn ọ̀rọ̀ ẹnu mi.

 2 Màá la ẹnu mi láti pa òwe.

Màá pa àwọn àlọ́ tó ti wà tipẹ́tipẹ́.+

 3 Àwọn ohun tí a ti gbọ́ tí a sì mọ̀,

Èyí tí àwọn bàbá wa sọ fún wa,+

 4 A ò ní fi wọ́n pa mọ́ fún àwọn ọmọ wọn;

A ó ròyìn fún ìran tó ń bọ̀+

Nípa àwọn iṣẹ́ Jèhófà tó yẹ fún ìyìn àti nípa agbára rẹ̀,+

Àwọn ohun àgbàyanu tó ti ṣe.+

 5 Ó gbé ìránnilétí kan kalẹ̀ ní Jékọ́bù,

Ó sì ṣe òfin ní Ísírẹ́lì;

Ó pa àṣẹ fún àwọn baba ńlá wa

Pé kí wọ́n jẹ́ kí àwọn ọmọ wọn mọ àwọn nǹkan yìí,+

 6 Kí ìran tó ń bọ̀,

Ìyẹn àwọn ọmọ tí wọ́n máa bí, lè mọ̀ wọ́n.+

Kí àwọn náà lè ròyìn wọn fún àwọn ọmọ wọn.+

 7 Àwọn yìí á wá gbẹ́kẹ̀ lé Ọlọ́run.

Wọn ò ní gbàgbé àwọn iṣẹ́ Ọlọ́run+

Kàkà bẹ́ẹ̀, wọ́n á máa pa àwọn àṣẹ rẹ̀ mọ́.+

 8 Wọn ò ní dà bí àwọn baba ńlá wọn,

Ìran alágídí àti ọlọ̀tẹ̀,+

Ìran tí ọkàn wọn ń ṣe ségesège*+

Tí ẹ̀mí wọn ò sì jẹ́ olóòótọ́ sí Ọlọ́run.

 9 Àwọn ọmọ Éfúrémù kó ọfà* dání,

Àmọ́ wọ́n sá pa dà lọ́jọ́ ogun.

10 Wọn ò pa májẹ̀mú Ọlọ́run mọ́,+

Wọn ò sì tẹ̀ lé òfin rẹ̀.+

11 Wọ́n tún gbàgbé ohun tó ti ṣe,+

Àwọn iṣẹ́ àgbàyanu tó fi hàn wọ́n.+

12 Ó ṣe àwọn ohun àgbàyanu níwájú àwọn baba ńlá wọn,+

Ní ilẹ̀ Íjíbítì, ní agbègbè Sóánì.+

13 Ó pín òkun sọ́tọ̀, kí wọ́n lè gbà á kọjá,

Ó sì mú kí omi òkun dúró bí ìsédò.*+

14 Ó fi ìkùukùu* ṣamọ̀nà wọn ní ọ̀sán,

Ó sì fi ìmọ́lẹ̀ iná ṣamọ̀nà wọn ní gbogbo òru.+

15 Ó la àpáta ní aginjù,

Ó jẹ́ kí wọ́n mu àmutẹ́rùn bíi pé látinú ibú omi.+

16 Ó mú kí omi ṣàn jáde látinú àpáta,

Ó sì mú kí omi ṣàn wálẹ̀ bí odò.+

17 Àmọ́ wọ́n ń dẹ́ṣẹ̀ sí i nìṣó,

Bí wọ́n ṣe ń ṣọ̀tẹ̀ sí Ẹni Gíga Jù Lọ ní aṣálẹ̀;+

18 Wọ́n pe Ọlọ́run níjà* nínú ọkàn wọn,+

Bí wọ́n ṣe ń béèrè oúnjẹ tí ọkàn wọn fà sí.*

19 Wọ́n sọ̀rọ̀ òdì sí Ọlọ́run,

Wọ́n ní: “Ṣé Ọlọ́run lè tẹ́ tábìlì nínú aginjù ni?”+

20 Wò ó! Ó lu àpáta

Kí omi lè ṣàn, kí odò sì ya jáde.+

Síbẹ̀ wọ́n ń sọ pé, “Ṣé ó tún lè fún wa ní oúnjẹ ni,

Àbí ṣé ó lè pèsè ẹran fún àwọn èèyàn rẹ̀?”+

21 Nígbà tí Jèhófà gbọ́ wọn, inú bí i gan-an;+

Iná+ jó Jékọ́bù,

Inú rẹ̀ sì ru sí Ísírẹ́lì.+

22 Torí pé wọn ò ní ìgbàgbọ́ nínú Ọlọ́run;+

Wọn ò gbẹ́kẹ̀ lé e pé ó lágbára láti gbà wọ́n là.

23 Torí náà, ó pàṣẹ fún ojú ọ̀run tó ṣú dẹ̀dẹ̀ lókè,

Ó sì ṣí àwọn ilẹ̀kùn ọ̀run.

24 Ó ń rọ̀jò mánà sílẹ̀ fún wọn láti jẹ;

Ó fún wọn ní ọkà ọ̀run.+

25 Àwọn èèyàn jẹ oúnjẹ àwọn alágbára;*+

Ó pèsè èyí tó pọ̀ tó kí wọ́n lè jẹ àjẹyó.+

26 Ó ru ẹ̀fúùfù ìlà oòrùn sókè ní ọ̀run,

Ó sì mú kí ẹ̀fúùfù gúúsù fẹ́ nípasẹ̀ agbára rẹ̀.+

27 Ó rọ̀jò ẹran lé wọn lórí bí eruku,

Àwọn ẹyẹ bí iyanrìn etíkun.

28 Ó mú kí wọ́n já bọ́ sí àárín ibùdó rẹ̀,

Káàkiri àwọn àgọ́ rẹ̀.

29 Wọ́n jẹ àjẹyó àti àjẹkì;

Ó fún wọn ní ohun tí ọkàn wọn fẹ́.+

30 Àmọ́ kí wọ́n tó tẹ́ ìfẹ́ ọkàn wọn lọ́rùn pátápátá,

Nígbà tí oúnjẹ wọn ṣì wà lẹ́nu wọn,

 31 Ìbínú Ọlọ́run ru sí wọn.+

Ó pa àwọn ọkùnrin wọn tó lágbára jù lọ;+

Ó mú àwọn ọ̀dọ́kùnrin Ísírẹ́lì balẹ̀.

32 Láìka gbogbo èyí sí, ṣe ni wọ́n ń dá ẹ̀ṣẹ̀ lé ẹ̀ṣẹ̀,+

Wọn ò sì ní ìgbàgbọ́ nínú àwọn iṣẹ́ àgbàyanu rẹ̀.+

33 Torí náà, ó fòpin sí ọjọ́ ayé wọn bíi pé èémí lásán ni,+

Ó sì fòpin sí ọdún wọn nípasẹ̀ àjálù òjijì.

34 Àmọ́ tó bá ti bẹ̀rẹ̀ sí í pa wọ́n, wọ́n á wá a;+

Wọ́n á pa dà, wọ́n á sì wá Ọlọ́run,

 35 Wọ́n á rántí pé Ọlọ́run ni Àpáta wọn+

Àti pé Ọlọ́run Ẹni Gíga Jù Lọ ni Olùdáǹdè* wọn.+

36 Àmọ́ wọ́n fẹ́ fi ẹnu wọn tàn án jẹ,

Kí wọ́n sì fi ahọ́n wọn parọ́ fún un.

37 Ọkàn wọn ò ṣe déédéé pẹ̀lú rẹ̀;+

Wọn ò sì pa májẹ̀mú rẹ̀ mọ́.+

38 Àmọ́, ó jẹ́ aláàánú;+

Ó máa ń dárí ẹ̀ṣẹ̀ wọn jì wọ́n,* kò sì ní pa wọ́n run.+

Ó máa ń fawọ́ ìbínú rẹ̀ sẹ́yìn lọ́pọ̀ ìgbà,+

Kàkà tí ì bá fi jẹ́ kí gbogbo ìbínú rẹ̀ ru.

39 Nítorí ó rántí pé ẹlẹ́ran ara ni wọ́n,+

Afẹ́fẹ́ tó ń fẹ́ kọjá, tí kì í sì í pa dà wá.*

40 Ẹ wo iye ìgbà tí wọ́n ṣọ̀tẹ̀ sí i ní aginjù,+

Tí wọ́n sì bà á nínú jẹ́ ní aṣálẹ̀!+

41 Léraléra ni wọ́n dán Ọlọ́run wò,+

Wọ́n sì kó ẹ̀dùn ọkàn bá* Ẹni Mímọ́ Ísírẹ́lì.

42 Wọn ò rántí agbára* rẹ̀,

Lọ́jọ́ tó gbà wọ́n* lọ́wọ́ ọ̀tá,+

 43 Bó ṣe fi àwọn iṣẹ́ àmì rẹ̀ hàn ní Íjíbítì+

Àti àwọn iṣẹ́ ìyanu rẹ̀ ní agbègbè Sóánì,

 44 Àti bó ṣe sọ àwọn ipa odò Náílì di ẹ̀jẹ̀,+

Tí wọn ò fi lè mu omi àwọn odò wọn.

45 Ó rán ọ̀wọ́ eṣinṣin mùjẹ̀mùjẹ̀ láti jẹ wọ́n run+

Àti àwọn àkèré láti ba ilẹ̀ wọn jẹ́.+

46 Ó fi àwọn ohun ọ̀gbìn wọn fún àwọn ọ̀yánnú eéṣú,

Ó sì fi èso iṣẹ́ wọn fún ọ̀wọ́ eéṣú.+

47 Ó fi yìnyín pa àjàrà wọn run,+

Ó sì fi àwọn òkúta yìnyín pa àwọn igi síkámórè wọn.

48 Ó fi yìnyín pa àwọn ẹran akẹ́rù wọn,+

Ó sì sán ààrá* pa àwọn ẹran ọ̀sìn wọn.

49 Ó tú ìbínú rẹ̀ tó ń jó bí iná lé wọn lórí,

Ìbínú ńlá àti ìrunú àti wàhálà,

Ó rán àwùjọ àwọn áńgẹ́lì láti mú àjálù wá.

50 Ó la ọ̀nà fún ìbínú rẹ̀.

Kò dá wọn* sí;

Ó sì fi wọ́n* lé àjàkálẹ̀ àrùn lọ́wọ́.

51 Níkẹyìn, ó pa gbogbo àkọ́bí Íjíbítì,+

Ìbẹ̀rẹ̀ agbára ìbímọ wọn nínú àwọn àgọ́ Hámù.

52 Lẹ́yìn náà, ó mú àwọn èèyàn rẹ̀ jáde bí agbo ẹran,+

Ó sì darí wọn bí ọ̀wọ́ ẹran ní aginjù.

53 Ó darí wọn láìséwu,

Wọn ò sì bẹ̀rù ohunkóhun;+

Òkun bo àwọn ọ̀tá wọn mọ́lẹ̀.+

54 Ó mú wọn wá sí ìpínlẹ̀ mímọ́ rẹ̀,+

Agbègbè olókè tí ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ gbà.+

55 Ó lé àwọn orílẹ̀-èdè jáde níwájú wọn;+

Ó fi okùn ìdíwọ̀n pín ogún fún wọn;+

Ó mú kí àwọn ẹ̀yà Ísírẹ́lì máa gbé inú ilé wọn.+

56 Àmọ́ wọn ò yéé pe Ọlọ́run Ẹni Gíga Jù Lọ níjà,* wọ́n sì ń ṣọ̀tẹ̀ sí i;+

Wọn ò fiyè sí àwọn ìránnilétí rẹ̀.+

57 Yàtọ̀ síyẹn, wọ́n yíjú pa dà, wọ́n sì di oníbékebèke bí àwọn baba ńlá wọn.+

Wọ́n dà bí ọrun dídẹ̀ tí kò ṣeé gbára lé.+

58 Wọ́n ń fi àwọn ibi gíga wọn mú un bínú ṣáá,+

Wọ́n sì fi àwọn ère gbígbẹ́ wọn mú kí ìbínú rẹ̀ ru.*+

59 Ọlọ́run gbọ́, inú sì bí i gidigidi,+

Torí náà, ó kọ Ísírẹ́lì sílẹ̀ pátápátá.

60 Níkẹyìn, ó pa àgọ́ ìjọsìn Ṣílò tì,+

Àgọ́ tí ó gbé inú rẹ̀ láàárín àwọn èèyàn.+

61 Ó jẹ́ kí àmì agbára rẹ̀ lọ sóko ẹrú;

Ó jẹ́ kí ọlá ńlá rẹ̀ bọ́ sọ́wọ́ àwọn ọ̀tá.+

62 Ó jẹ́ kí wọ́n fi idà pa àwọn èèyàn rẹ̀,+

Inú sì bí i gidigidi sí ogún rẹ̀.

63 Iná jó àwọn ọ̀dọ́kùnrin rẹ̀ run,

A kò sì kọ orin ìgbéyàwó fún* àwọn wúńdíá rẹ̀.

64 Wọ́n fi idà pa àwọn àlùfáà rẹ̀,+

Àwọn opó wọn ò sì sunkún.+

65 Nígbà náà, Jèhófà jí bíi pé láti ojú oorun,+

Bí akíkanjú ọkùnrin+ tí wáìnì dá lójú rẹ̀ nígbà tó jí.

66 Ó lé àwọn ọ̀tá rẹ̀ pa dà;+

Ó mú kí ìtìjú ayérayé bá wọn.

67 Ó kọ àgọ́ Jósẹ́fù sílẹ̀;

Kò sì yan ẹ̀yà Éfúrémù.

68 Àmọ́, ó yan ẹ̀yà Júdà,+

Òkè Síónì, èyí tí ó nífẹ̀ẹ́.+

69 Ó mú kí ibi mímọ́ rẹ̀ lè máa wà títí lọ bí ọ̀run,*+

Bí ayé tí ó fìdí rẹ̀ múlẹ̀ títí láé.+

70 Ó yan Dáfídì+ ìránṣẹ́ rẹ̀,

Ó sì mú un kúrò nínú ọgbà àgùntàn,+

71 Kúrò ní ibi tó ti ń tọ́jú àwọn abo àgùntàn tó ń fọ́mọ lọ́mú;

Ó fi í ṣe olùṣọ́ àgùntàn lórí Jékọ́bù, àwọn èèyàn rẹ̀+

Àti lórí Ísírẹ́lì, ogún rẹ̀.+

72 Ó fi òtítọ́ ọkàn ṣe olùṣọ́ àgùntàn wọn,+

Ó sì darí wọn lọ́nà tó já fáfá.+

Orin Ásáfù.+

79 Ọlọ́run, àwọn orílẹ̀-èdè ti ya wọnú ogún rẹ;+

Wọ́n ti sọ tẹ́ńpìlì mímọ́ rẹ di ẹlẹ́gbin;+

Wọ́n ti sọ Jerúsálẹ́mù di àwókù.+

 2 Wọ́n ti fi òkú àwọn ìránṣẹ́ rẹ ṣe oúnjẹ fún àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run,

Wọ́n sì ti fi ẹran ara àwọn ẹni ìdúróṣinṣin rẹ fún àwọn ẹran inú igbó.+

 3 Wọ́n ti da ẹ̀jẹ̀ wọn sílẹ̀ bí omi káàkiri Jerúsálẹ́mù,

Kò sì sí ẹni tó ṣẹ́ kù tó máa sin wọ́n.+

 4 A ti di ẹni ẹ̀gàn lójú àwọn aládùúgbò wa;+

Àwọn tó yí wa ká ń fi wá ṣẹ̀sín, wọ́n sì ń fi wá ṣe yẹ̀yẹ́.

 5 Jèhófà, ìgbà wo lo máa bínú dà? Ṣé títí láé ni?+

Ìgbà wo ni ìbínú ńlá rẹ máa jó bí iná dà?+

 6 Da ìrunú rẹ sórí àwọn orílẹ̀-èdè tí kò mọ̀ ọ́

Àti sórí àwọn ìjọba tí kì í ké pe orúkọ rẹ.+

 7 Nítorí wọ́n ti jẹ Jékọ́bù run,

Wọ́n sì ti sọ ìlú ìbílẹ̀ rẹ̀ di ahoro.+

 8 Má ṣe ka ẹ̀ṣẹ̀ àwọn baba ńlá wa sí wa lọ́rùn.+

Tètè wá ṣàánú wa,+

Torí wọ́n ti bá wa kanlẹ̀.

 9 Ràn wá lọ́wọ́, Ọlọ́run ìgbàlà wa,+

Nítorí orúkọ rẹ ológo;

Gbà wá sílẹ̀, kí o sì dárí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa jì wá* nítorí orúkọ rẹ.+

10 Kí nìdí tí àwọn orílẹ̀-èdè á fi sọ pé: “Ọlọ́run wọn dà?”+

Níṣojú wa, jẹ́ kí àwọn orílẹ̀-èdè mọ̀ pé

O ti gbẹ̀san ẹ̀jẹ̀ àwọn ìránṣẹ́ rẹ tí wọ́n ta sílẹ̀.+

11 Gbọ́ ìkérora àwọn ẹlẹ́wọ̀n.+

Fi agbára ńlá* rẹ dáàbò bo* àwọn tí wọ́n ti dájọ́ ikú fún.*+

12 San án pa dà fún àwọn aládùúgbò wa ní ìlọ́po méje+

Nítorí ẹ̀gàn tí wọ́n kó bá ọ, Jèhófà.+

13 Nígbà náà, àwa èèyàn rẹ àti agbo ẹran ibi ìjẹko rẹ+

Yóò máa fi ọpẹ́ fún ọ títí láé;

A ó sì máa kéde ìyìn rẹ láti ìran dé ìran.+

Sí olùdarí; kí a yí i sí “Òdòdó Lílì.” Ìránnilétí. Ti Ásáfù.+ Orin.

80 Fetí sílẹ̀, ìwọ Olùṣọ́ Àgùntàn Ísírẹ́lì,

Ìwọ tí ò ń darí Jósẹ́fù bí agbo ẹran.+

Ìwọ tí ò ń jókòó lórí* àwọn kérúbù,+

Máa tàn yanran.*

 2 Níwájú Éfúrémù àti Bẹ́ńjámínì àti Mánásè,

Fi agbára ńlá rẹ hàn;+

Wá gbà wá là.+

 3 Ọlọ́run, mú wa bọ̀ sípò;+

Jẹ́ kí ojú rẹ tàn sí wa lára, kí a lè rí ìgbàlà.+

 4 Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun, ìgbà wo lo máa bínú* sí àdúrà àwọn èèyàn rẹ dà?+

 5 O fi omijé bọ́ wọn bí oúnjẹ,

O sì mú kí wọ́n mu omijé tí kò ṣeé díwọ̀n.

 6 O jẹ́ kí àwọn aládùúgbò wa máa jà torí kí wọ́n lè borí wa;

Àwọn ọ̀tá wa ń fi wá ṣẹ̀sín bó ṣe wù wọ́n.+

 7 Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun, mú wa bọ̀ sípò;

Jẹ́ kí ojú rẹ tàn sí wa lára, kí a lè rí ìgbàlà.+

 8 O mú kí àjàrà+ kan kúrò ní Íjíbítì.

O lé àwọn orílẹ̀-èdè jáde, o sì gbin àjàrà náà.+

 9 O ro ilẹ̀ fún un,

Ó ta gbòǹgbò, ó sì kún ilẹ̀ náà.+

10 Òjìji rẹ̀ bo àwọn òkè mọ́lẹ̀,

Àwọn ẹ̀ka rẹ̀ sì bo àwọn igi kédárì Ọlọ́run mọ́lẹ̀.

11 Àwọn ẹ̀ka rẹ̀ nà títí dé òkun,

Àwọn ẹ̀tun rẹ̀ sì dé Odò.*+

12 Kí nìdí tí o fi wó ògiri olókùúta ọgbà àjàrà náà lulẹ̀,+

Tí gbogbo àwọn tó ń kọjá lọ fi ń ká èso rẹ̀?+

13 Àwọn ẹlẹ́dẹ̀ igbó* ń bà á jẹ́,

Àwọn ẹranko inú igbó sì ń jẹ ẹ́.+

14 Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun, jọ̀wọ́ pa dà.

Bojú wolẹ̀ láti ọ̀run, kí o sì rí i!

Bójú tó àjàrà yìí,+

15 Kùkùté* tí ọwọ́ ọ̀tún rẹ gbìn,+

Kí o sì wo ọmọ* tí o sọ di alágbára fún ògo rẹ.+

16 Wọ́n ti dáná sun ún,+ wọ́n sì gé e lulẹ̀.

Nígbà tí o bá wọn wí,* wọ́n ṣègbé.

17 Kí ọwọ́ rẹ fún ọkùnrin tó wà lọ́wọ́ ọ̀tún rẹ lókun,

Kí ọwọ́ rẹ fi okun fún ọmọ èèyàn tí o sọ di alágbára fún ara rẹ.+

18 Nígbà náà, a kò ní yí pa dà kúrò lọ́dọ̀ rẹ.

Mú kí á máa wà láàyè, kí a lè máa ké pe orúkọ rẹ.

19 Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun, mú wa bọ̀ sípò;

Jẹ́ kí ojú rẹ tàn sí wa lára, kí a lè rí ìgbàlà.+

Sí olùdarí; lórí Gítítì.* Ti Ásáfù.+

81 Ẹ kígbe ayọ̀ sí Ọlọ́run tó jẹ́ agbára wa.+

Ẹ kígbe ìṣẹ́gun sí Ọlọ́run Jékọ́bù.

 2 Ẹ bẹ̀rẹ̀ orin, ẹ gbé ìlù tanboríìnì,

Háàpù tó ń dún dáadáa àti ohun ìkọrin olókùn tín-ín-rín.

 3 Ẹ fun ìwo nígbà òṣùpá tuntun,+

Nígbà òṣùpá àrànmọ́jú, nítorí ọjọ́ àjọyọ̀ wa.+

 4 Nítorí pé òfin ló jẹ́ fún Ísírẹ́lì,

Àṣẹ Ọlọ́run Jékọ́bù.+

 5 Ó fi í ṣe ìrántí fún Jósẹ́fù+

Nígbà tí Ó jáde lọ láti dojú kọ ilẹ̀ Íjíbítì.+

Mo gbọ́ ohùn* kan tí mi ò mọ̀, tó sọ pé:

 6 “Mo gbé ẹrù kúrò ní èjìká rẹ̀;+

Mo gba apẹ̀rẹ̀ kúrò lọ́wọ́ rẹ̀.

 7 O pè mí nínú wàhálà tó bá ọ, mo sì gbà ọ́ sílẹ̀;+

Mo dá ọ lóhùn láti ojú ọ̀run tó ń sán ààrá.*+

Mo dán ọ wò níbi omi Mẹ́ríbà.*+ (Sélà)

 8 Ẹ gbọ́, ẹ̀yin èèyàn mi, màá ta kò yín.

Ìwọ Ísírẹ́lì, ká ní o lè fetí sí mi.+

 9 Kò ní sí ọlọ́run àjèjì láàárín rẹ,

O kò sì ní forí balẹ̀ fún ọlọ́run ilẹ̀ òkèèrè.+

10 Èmi, Jèhófà, ni Ọlọ́run rẹ,

Ẹni tó mú ọ jáde kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì.+

La gbogbo ẹnu rẹ, màá sì fi oúnjẹ kún un.+

11 Àmọ́ àwọn èèyàn mi ò fetí sí ohùn mi;

Ísírẹ́lì kò ṣègbọràn sí mi.+

12 Torí náà, mo jẹ́ kí wọ́n máa ṣe ohun tí agídí ọkàn wọn sọ;

Wọ́n ń ṣe ohun tí wọ́n rò pé ó tọ́.*+

13 Ká ní àwọn èèyàn mi lè fetí sí mi,+

Ká ní Ísírẹ́lì lè rìn ní àwọn ọ̀nà mi!+

14 Kíákíá ni mi ò bá ṣẹ́gun àwọn ọ̀tá wọn;

Mi ò bá yí ọwọ́ mi pa dà sí àwọn elénìní wọn.+

15 Àwọn tó kórìíra Jèhófà yóò ba búrúbúrú níwájú rẹ̀,

Ohun tó máa ṣẹlẹ̀ sí wọn* yóò sì wà títí láé.

16 Àmọ́ yóò fi àlìkámà* tó dára jù lọ* bọ́ ọ,*+

Yóò sì fi oyin inú àpáta tẹ́ ọ lọ́rùn.”+

Orin Ásáfù.+

82 Ọlọ́run dúró sí àyè rẹ̀ nínú àpéjọ ọ̀run;*+

Ó ń ṣe ìdájọ́ ní àárín àwọn ọlọ́run*+ pé:

 2 “Títí dìgbà wo ni ẹ ó máa fi àìṣòdodo dá ẹjọ́,+

Tí ẹ ó sì máa ṣe ojúsàájú àwọn ẹni burúkú?+ (Sélà)

 3 Ẹ gbèjà* aláìní àti ọmọ aláìníbaba.+

Ẹ dá ẹjọ́ ẹni tí ìyà ń jẹ àti òtòṣì bó ṣe tọ́.+

 4 Ẹ gba aláìní àti tálákà sílẹ̀;

Ẹ gbà wọ́n lọ́wọ́ àwọn ẹni burúkú.”

 5 Wọn ò mọ̀, kò sì yé wọn;+

Wọ́n ń rìn kiri nínú òkùnkùn;

Gbogbo ìpìlẹ̀ ayé ń mì tìtì.+

 6 “Mo sọ pé, ‘ọlọ́run* ni yín,+

Gbogbo yín jẹ́ ọmọ Ẹni Gíga Jù Lọ.

 7 Àmọ́, ẹ̀yin yóò kú bí àwọn èèyàn ṣe ń kú;+

Ẹ ó sì ṣubú bí àwọn olórí ṣe ń ṣubú!’”+

 8 Dìde, Ọlọ́run, ṣe ìdájọ́ ayé,+

Nítorí gbogbo orílẹ̀-èdè jẹ́ tìrẹ.

Orin. Orin Ásáfù.+

83 Ọlọ́run, má ṣe dákẹ́;+

Má ṣàìsọ̀rọ̀,* má sì dúró jẹ́ẹ́, ìwọ Olú Ọ̀run.

 2 Wò ó! àwọn ọ̀tá rẹ wà nínú rúkèrúdò;+

Àwọn tó kórìíra rẹ ń hùwà ìgbéraga.*

 3 Wọ́n fi ọgbọ́nkọ́gbọ́n gbìmọ̀ pọ̀ nítorí àwọn èèyàn rẹ;

Wọ́n sì lẹ̀dí àpò pọ̀ nítorí àwọn àyànfẹ́ rẹ.*

 4 Wọ́n sọ pé: “Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí a pa wọ́n run kí wọ́n má ṣe jẹ́ orílẹ̀-èdè mọ́,+

Kí a má sì rántí orúkọ Ísírẹ́lì mọ́.”

 5 Wọ́n fohùn ṣọ̀kan lórí ohun tí wọ́n máa ṣe;*

Wọ́n gbìmọ̀ pọ̀* láti bá ọ jà,+

 6 Àgọ́ Édómù àti ti àwọn ọmọ Íṣímáẹ́lì, Móábù+ àti àwọn ọmọ Hágárì,+

 7 Gébálì àti Ámónì+ àti Ámálékì,

Filísíà+ pẹ̀lú àwọn tó ń gbé ní Tírè.+

 8 Ásíríà+ pẹ̀lú ti dara pọ̀ mọ́ wọn;

Wọ́n ran àwọn ọmọ Lọ́ọ̀tì+ lọ́wọ́.* (Sélà)

 9 Kí o ṣe wọ́n bí o ti ṣe Mídíánì,+

Bí o ti ṣe Sísérà àti Jábínì ní odò* Kíṣónì.+

10 Wọ́n pa run ní Ẹ́ń-dórì;+

Wọ́n di ajílẹ̀ fún ilẹ̀.

11 Ṣe àwọn èèyàn pàtàkì wọn bí Órébù àti Séébù,+

Kí o sì ṣe àwọn olórí* wọn bíi Séébà àti Sálímúnà,+

12 Nítorí wọ́n sọ pé: “Ẹ jẹ́ kí a gba ilẹ̀ tí Ọlọ́run ń gbé.”

13 Ìwọ Ọlọ́run mi, ṣe wọ́n bí ẹ̀gún tí afẹ́fẹ́ ń fẹ́ yípo yípo,*+

Bí àgékù pòròpórò tí afẹ́fẹ́ ń fẹ́ kiri.

14 Bí iná tó ń jó igbó

Àti bí ọwọ́ iná tó ń jó àwọn òkè,+

15 Bẹ́ẹ̀ ni kí o fi ìjì líle rẹ lépa wọn,+

Kí o sì fi ẹ̀fúùfù rẹ kó jìnnìjìnnì bá wọn.+

16 Fi àbùkù bò wọ́n lójú,*

Kí wọ́n lè máa wá orúkọ rẹ, Jèhófà.

17 Kí ojú tì wọ́n, kí jìnnìjìnnì sì bá wọn títí láé;

Kí wọ́n tẹ́, kí wọ́n sì ṣègbé;

18 Kí àwọn èèyàn lè mọ̀ pé ìwọ, ẹni tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Jèhófà,+

Ìwọ nìkan ṣoṣo ni Ẹni Gíga Jù Lọ lórí gbogbo ayé.+

Fún olùdarí; lórí Gítítì.* Ti àwọn ọmọ Kórà.+ Orin.

84 Àgọ́ ìjọsìn rẹ títóbi lọ́lá mà dára o,*+

Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun!

 2 Àárò ń sọ mí,*

Àní, àárẹ̀ ti mú mi bó ṣe ń wù mí

Láti wá sí àwọn àgbàlá Jèhófà.+

Gbogbo ọkàn àti gbogbo ara mi ni mo fi ń kígbe ayọ̀ sí Ọlọ́run alààyè.

 3 Kódà ẹyẹ rí ilé síbẹ̀,

Alápàáǹdẹ̀dẹ̀ sì rí ìtẹ́ fún ara rẹ̀,

Ibẹ̀ ló ti ń tọ́jú àwọn ọmọ rẹ̀

Nítòsí pẹpẹ rẹ títóbi lọ́lá, Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun,

Ọba mi àti Ọlọ́run mi!

 4 Aláyọ̀ ni àwọn tó ń gbé inú ilé rẹ!+

Wọ́n ń yìn ọ́ nígbà gbogbo.+ (Sélà)

 5 Aláyọ̀ ni àwọn tó fi ọ́ ṣe agbára wọn,+

Àwọn tí ọkàn wọn wà ní ọ̀nà tó lọ sí ilé rẹ.

 6 Nígbà tí wọ́n gba Àfonífojì Bákà* kọjá,

Wọ́n sọ ibẹ̀ di ibi ìsun omi;

Òjò àkọ́rọ̀ sì fi ìbùkún rin ín.*

 7 Wọ́n á máa ti inú agbára bọ́ sínú agbára;+

Kálukú wọn ń wá síwájú Ọlọ́run ní Síónì.

 8 Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun, gbọ́ àdúrà mi;

Fetí sílẹ̀, ìwọ Ọlọ́run Jékọ́bù. (Sélà)

 9 Kíyè sí i, ìwọ apata+ wa àti Ọlọ́run wa,*

Wo ojú ẹni àmì òróró rẹ.+

10 Nítorí ọjọ́ kan nínú àwọn àgbàlá rẹ sàn ju ẹgbẹ̀rún ọjọ́ níbikíbi!+

Mo yàn láti máa dúró níbi àbáwọlé ilé Ọlọ́run mi

Dípò kí n máa gbé inú àgọ́ àwọn èèyàn burúkú.

11 Nítorí Jèhófà Ọlọ́run jẹ́ oòrùn+ àti apata;+

Ó ń ṣojú rere síni, ó sì ń fúnni ní ògo.

Jèhófà kò ní fawọ́ ohun rere sẹ́yìn

Lọ́dọ̀ àwọn tó ń rìn nínú ìwà títọ́.+

12 Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun,

Aláyọ̀ ni ẹni tó gbẹ́kẹ̀ lé ọ.+

Fún olùdarí. Ti àwọn ọmọ Kórà.+ Orin.

85 Jèhófà, o ti ṣojú rere sí ilẹ̀ rẹ;+

O mú àwọn tí wọ́n kó lẹ́rú+ lára Jékọ́bù pa dà wá.

 2 O ti gbójú fo àṣìṣe àwọn èèyàn rẹ;

O dárí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ wọn jì wọ́n.*+ (Sélà)

 3 O fawọ́ gbogbo ìbínú rẹ tó ń jó bí iná sẹ́yìn;

O yí pa dà kúrò nínú ìbínú gbígbóná rẹ.+

 4 Mú wa bọ̀ sípò,* Ọlọ́run ìgbàlà wa,

Kí o má sì bínú sí wa mọ́.+

 5 Ṣé títí láé ni wàá máa bínú sí wa ni?+

Ṣé wàá jẹ́ kí ìbínú rẹ máa lọ láti ìran dé ìran ni?

 6 Ṣé o ò ní mú wa sọ jí ni,

Kí àwọn èèyàn rẹ lè máa yọ̀ nínú rẹ?+

 7 Fi ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ hàn sí wa, Jèhófà,+

Kí o sì fún wa ní ìgbàlà rẹ.

 8 Màá fetí sí ohun tí Jèhófà Ọlọ́run tòótọ́ sọ,

Nítorí ó máa sọ̀rọ̀ àlàáfíà fún àwọn èèyàn rẹ̀,+ àwọn ẹni ìdúróṣinṣin rẹ̀,

Àmọ́ kí wọ́n má ṣe pa dà máa dá ara wọn lójú jù.+

 9 Ó dájú pé ìgbàlà rẹ̀ wà nítòsí àwọn tó bẹ̀rù rẹ̀,+

Kí ògo rẹ̀ lè máa gbé ní ilẹ̀ wa.

10 Ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ àti òtítọ́ yóò pàdé ara wọn;

Òdodo àti àlàáfíà yóò fi ẹnu ko ara wọn lẹ́nu.+

11 Òtítọ́ yóò rú jáde látinú ilẹ̀,

Òdodo yóò sì bojú wolẹ̀ láti ọ̀run.+

12 Bẹ́ẹ̀ ni, Jèhófà yóò pèsè ohun rere,*+

Ilẹ̀ wa yóò sì máa mú èso jáde.+

13 Òdodo yóò máa rìn níwájú rẹ̀,+

Yóò sì la ọ̀nà fún ìṣísẹ̀ rẹ̀.

Àdúrà Dáfídì.

86 Fetí sílẹ̀,* Jèhófà, kí o sì dá mi lóhùn,

Nítorí pé ìyà ń jẹ mí, mo sì jẹ́ aláìní.+

 2 Ṣọ́ ẹ̀mí* mi, torí pé adúróṣinṣin+ ni mí.

Gba ìránṣẹ́ rẹ tó gbẹ́kẹ̀ lé ọ là,

Nítorí ìwọ ni Ọlọ́run mi.+

 3 Ṣojú rere sí mi, Jèhófà,+

Nítorí ìwọ ni mò ń ké pè láti àárọ̀ ṣúlẹ̀.+

 4 Mú kí ìránṣẹ́ rẹ* máa yọ̀,

Nítorí ọ̀dọ̀ rẹ ni mo yíjú* sí, Jèhófà.

 5 Nítorí pé ẹni rere ni ọ́,+ Jèhófà, o sì ṣe tán láti dárí jini;+

Ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ tí o ní sí gbogbo àwọn tó ń ké pè ọ́ pọ̀ gidigidi.+

 6 Jèhófà, gbọ́ àdúrà mi;

Sì fetí sí ẹ̀bẹ̀ mi fún ìrànlọ́wọ́.+

 7 Mo ké pè ọ́ ní ọjọ́ wàhálà mi,+

Torí mo mọ̀ pé wàá dá mi lóhùn.+

 8 Jèhófà, kò sí èyí tó dà bí rẹ nínú àwọn ọlọ́run,+

Kò sí iṣẹ́ kankan tó dà bíi tìrẹ.+

 9 Gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè tí o dá

Yóò wá forí balẹ̀ níwájú rẹ, Jèhófà,+

Wọn yóò sì fi ògo fún orúkọ rẹ.+

10 Nítorí ẹni ńlá ni ọ́, o sì ń ṣe àwọn ohun àgbàyanu;+

Ìwọ ni Ọlọ́run, ìwọ nìkan ṣoṣo.+

11 Jèhófà, kọ́ mi ní ọ̀nà rẹ.+

Èmi yóò máa rìn nínú òtítọ́ rẹ.+

Fún mi ní ọkàn tó pa pọ̀* kí n lè máa bẹ̀rù orúkọ rẹ.+

12 Mo fi gbogbo ọkàn mi yìn ọ́, Jèhófà Ọlọ́run mi,+

Màá sì máa yin orúkọ rẹ lógo títí láé,

13 Nítorí ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ tí o ní sí mi pọ̀,

O sì ti gba ẹ̀mí* mi lọ́wọ́ Isà Òkú.*+

14 Ọlọ́run, àwọn agbéraga dìde sí mi;+

Àwùjọ ìkà ẹ̀dá ń wá ọ̀nà láti gba ẹ̀mí* mi,

Wọn ò sì kà ọ́ sí.*+

15 Àmọ́ ní tìrẹ, Jèhófà, o jẹ́ Ọlọ́run aláàánú, tó ń gba tẹni rò,*

Tí kì í tètè bínú, tí ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ àti òdodo* rẹ̀ sì pọ̀ gidigidi.+

16 Yíjú sí mi, kí o sì ṣojú rere sí mi.+

Fún ìránṣẹ́ rẹ ní agbára,+

Kí o sì gba ọmọ ẹrúbìnrin rẹ là.

17 Fún mi ní àmì* oore rẹ,

Kí àwọn tó kórìíra mi lè rí i, kí ojú sì tì wọ́n.

Nítorí ìwọ Jèhófà ni olùrànlọ́wọ́ mi àti olùtùnú mi.

Ti àwọn ọmọ Kórà.+ Orin atunilára. Orin.

87 Ìpìlẹ̀ ìlú rẹ̀ wà lórí àwọn òkè mímọ́.+

 2 Jèhófà nífẹ̀ẹ́ àwọn ẹnubodè Síónì  +

Ju gbogbo àwọn àgọ́ Jékọ́bù lọ.

 3 Àwọn ohun ológo ni wọ́n ń sọ nípa rẹ, ìwọ ìlú Ọlọ́run tòótọ́.+ (Sélà)

 4 Màá ka Ráhábù+ àti Bábílónì mọ́ àwọn tó mọ̀ mí;*

Filísíà àti Tírè nìyí, pẹ̀lú Kúṣì.

Àwọn èèyàn á sọ pé: “Ẹni yìí ni a bí níbẹ̀.”

 5 Wọ́n á sọ nípa Síónì pé:

“Inú rẹ̀ ni a ti bí wọn lẹ́nì kọ̀ọ̀kan.”

Ẹni Gíga Jù Lọ yóò sì fìdí rẹ̀ múlẹ̀ ṣinṣin.

 6 Jèhófà yóò kéde nígbà tó bá ń ṣe àkọsílẹ̀ àwọn èèyàn náà pé:

“Ẹni yìí ni a bí níbẹ̀.” (Sélà)

 7 Àwọn akọrin+ àti àwọn tó ń jó ijó àjóyípo+ á sọ pé:

“Gbogbo ìsun omi mi wà nínú rẹ.”*+

Orin. Orin àwọn ọmọ Kórà.+ Sí olùdarí; lọ́nà ti Máhálátì,* kí a kọ ọ́ ní àkọgbà. Másíkílì* ti Hémánì+ tó jẹ́ Ẹ́síráhì.

88 Jèhófà, Ọlọ́run ìgbàlà mi,+

Mò ń ké ní ọ̀sán,

Mo sì ń wá síwájú rẹ ní òru.+

 2 Jẹ́ kí àdúrà mi wá síwájú rẹ,+

Fetí sí* igbe mi fún ìrànlọ́wọ́.+

 3 Nítorí pé wàhálà ti kún ọkàn* mi,+

Ẹ̀mí mi sì ti dé ẹnu Isà Òkú.*+

 4 Wọ́n ti kà mí mọ́ àwọn tó ń lọ sínú kòtò;*+

Mo ti di ẹni tí kò lè ṣe nǹkan kan,*+

 5 Tí wọ́n fi sílẹ̀ láàárín àwọn òkú,

Bí ẹni tí wọ́n pa, tó dùbúlẹ̀ sínú sàréè,

Ẹni tí o kò rántí mọ́,

Tí kò sì sí lábẹ́ àbójútó* rẹ mọ́.

 6 O ti fi mí sínú kòtò tó jìn jù lọ,

Ní ibi tó ṣókùnkùn, nínú ọ̀gbun ńlá tí kò nísàlẹ̀.

 7 Ìrunú rẹ pọ̀ lórí mi,+

O sì fi ìgbì rẹ tó ń pariwo bò mí mọ́lẹ̀. (Sélà)

 8 O ti lé àwọn ojúlùmọ̀ mi jìnnà réré sí mi;+

O ti sọ mí di ohun ìríra sí wọn.

Mo ti kó sí pańpẹ́, mi ò sì lè jáde.

 9 Ojú mi ti di bàìbàì nítorí ìyà tó ń jẹ mí.+

Mo ké pè ọ́, Jèhófà, láti àárọ̀ ṣúlẹ̀;+

Ìwọ ni mo tẹ́wọ́ àdúrà sí.

10 Ṣé àwọn òkú lo máa ṣe iṣẹ́ àgbàyanu hàn?

Ṣé àwọn tí ikú ti pa* lè dìde wá yìn ọ́?+ (Sélà)

11 Ṣé a lè kéde ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ nínú sàréè

Tàbí òtítọ́ rẹ ní ibi ìparun?*

12 Ṣé a lè mọ àwọn iṣẹ́ àgbàyanu rẹ nínú òkùnkùn

Tàbí òdodo rẹ ní ilẹ̀ àwọn ẹni ìgbàgbé?+

13 Síbẹ̀, Jèhófà, mò ń ké pè ọ́ fún ìrànlọ́wọ́,+

Àràárọ̀ ni àdúrà mi ń wá síwájú rẹ.+

14 Jèhófà, kí ló dé tí o fi kọ̀ mí* sílẹ̀?+

Kí ló dé tí o fi gbé ojú rẹ pa mọ́ fún mi?+

15 Láti ìgbà èwe mi

Ni ìyà ti ń jẹ mí, mo sì ti fẹ́rẹ̀ẹ́ kú;+

Àwọn àjálù tí o jẹ́ kó dé bá mi ti jẹ́ kí n kú sára.

16 Ìbínú rẹ tó ń jó bí iná bò mí mọ́lẹ̀;+

Jìnnìjìnnì láti ọ̀dọ̀ rẹ ti pa mí tán.

17 Wọ́n yí mi ká bí omi láti àárọ̀ ṣúlẹ̀;

Wọ́n gba ibi gbogbo yọ sí mi, wọ́n sì ká mi mọ́.*

18 O ti lé àwọn ọ̀rẹ́ mi àti àwọn alábàákẹ́gbẹ́ mi jìnnà réré sí mi;+

Òkùnkùn ti di alábàákẹ́gbẹ́ mi.

Másíkílì.* Ti Étánì+ tó jẹ́ Ẹ́síráhì.

89 Títí ayé ni èmi yóò máa kọ orin nípa bí Jèhófà ṣe ń fi ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ hàn.

Màá fi ẹnu mi sọ nípa òtítọ́ rẹ̀ fún gbogbo ìran.

 2 Nítorí mo sọ pé: “Ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ yóò dúró* títí láé,+

O ti mú kí òtítọ́ rẹ fìdí múlẹ̀ ṣinṣin ní ọ̀run.”

 3 “Mo ti bá àyànfẹ́ mi dá májẹ̀mú;+

Mo ti búra fún Dáfídì ìránṣẹ́ mi pé:+

 4 ‘Màá fìdí ọmọ* rẹ+ múlẹ̀ títí láé,

Màá gbé ìtẹ́ rẹ ró, á sì wà láti ìran dé ìran.’”+ (Sélà)

 5 Àwọn ọ̀run ń yin àwọn iṣẹ́ àgbàyanu rẹ, Jèhófà,

Àní, wọ́n ń yin òtítọ́ rẹ nínú ìjọ àwọn ẹni mímọ́.

 6 Ta ló wà ní ọ̀run tí a lè fi wé Jèhófà?+

Èwo nínú àwọn ọmọ Ọlọ́run+ ló dà bíi Jèhófà?

 7 Ọlọ́run yẹ lẹ́ni tí à ń bẹ̀rù nínú ìgbìmọ̀* àwọn ẹni mímọ́;+

Ó jẹ́ atóbilọ́lá àti ẹni tí ẹ̀rù rẹ̀ ń bani lójú gbogbo àwọn tó yí i ká.+

 8 Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun,

Ta ló lágbára bí rẹ, ìwọ Jáà?+

Òtítọ́ rẹ yí ọ ká.+

 9 Ò ń ṣàkóso ìrugùdù òkun;+

Nígbà tí ìgbì rẹ̀ ru sókè, o mú kí ó pa rọ́rọ́.+

10 O ti ṣẹ́gun Ráhábù+ pátápátá bí ẹni tí wọ́n pa.+

O ti fi apá rẹ tó lágbára tú àwọn ọ̀tá rẹ ká.+

11 Tìrẹ ni ọ̀run, tìrẹ sì ni ayé;+

Ilẹ̀ tó ń méso jáde àti ohun tó kún inú rẹ̀,+ ìwọ lo fìdí wọn múlẹ̀.

12 Ìwọ lo dá àríwá àti gúúsù;

Òkè Tábórì+ àti Hámónì+ ń fi ìdùnnú yin orúkọ rẹ.

13 Apá rẹ lágbára;+

Ọwọ́ rẹ lókun,+

Ọwọ́ ọ̀tún rẹ sì ga sókè.+

14 Òdodo àti ìdájọ́ òdodo ni ìpìlẹ̀ ìtẹ́ rẹ;+

Ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ àti òtítọ́ dúró níwájú rẹ.+

15 Aláyọ̀ ni àwọn tó ń fi ìdùnnú yìn ọ́.+

Jèhófà, inú ìmọ́lẹ̀ ojú rẹ ni wọ́n ti ń rìn.

16 Orúkọ rẹ ń mú inú wọn dùn láti àárọ̀ ṣúlẹ̀,

A sì gbé wọn ga nínú òdodo rẹ.

17 Nítorí ìwọ ni ògo agbára wọn,+

A sì gbé agbára* wa ga torí pé o tẹ́wọ́ gbà wá.+

18 Apata wa jẹ́ ti Jèhófà,

Ọba wa sì jẹ́ ti Ẹni Mímọ́ Ísírẹ́lì.+

19 Ní àkókò yẹn, o bá àwọn ẹni ìdúróṣinṣin rẹ sọ̀rọ̀ nínú ìran, o ní:

“Mo ti fún alágbára ní okun,+

Mo sì ti gbé àyànfẹ́ ga láàárín àwọn èèyàn.+

20 Mo ti rí Dáfídì ìránṣẹ́ mi;+

Mo ti fi òróró mímọ́ mi yàn án.+

21 Ọwọ́ mi yóò tì í lẹ́yìn,+

Apá mi yóò sì fún un lókun.

22 Ọ̀tá kankan kò ní gba ìṣákọ́lẹ̀* lọ́wọ́ rẹ̀,

Aláìṣòdodo kankan kò sì ní fìyà jẹ ẹ́.+

23 Màá fọ́ àwọn ọ̀tá rẹ̀ sí wẹ́wẹ́ níwájú rẹ̀,+

Màá sì ṣá àwọn tó kórìíra rẹ̀ balẹ̀.+

24 Òtítọ́ mi àti ìfẹ́ mi tí kì í yẹ̀ wà pẹ̀lú rẹ̀,+

A ó sì gbé agbára* rẹ̀ ga nítorí orúkọ mi.

25 Màá fi òkun sábẹ́ ọwọ́* rẹ̀,

Màá sì fi àwọn odò sábẹ́ ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀.+

26 Yóò ké pè mí pé: ‘Ìwọ ni Bàbá mi,

Ọlọ́run mi àti Àpáta ìgbàlà mi.’+

27 Èmi yóò fi í ṣe àkọ́bí,+

Ẹni tó ga jù lọ nínú àwọn ọba ayé.+

28 Èmi yóò máa fi ìfẹ́ mi tí kì í yẹ̀ hàn sí i títí láé,+

Májẹ̀mú tí mo bá a dá kò sì ní yẹ̀ láé.+

29 Màá fìdí àwọn ọmọ* rẹ̀ múlẹ̀ títí láé,

Màá sì mú kí ìtẹ́ rẹ̀ wà títí lọ bí ọ̀run.+

30 Tí àwọn ọmọ rẹ̀ bá pa òfin mi tì,

Tí wọn ò sì tẹ̀ lé àwọn àṣẹ* mi,

 31 Tí wọ́n bá rú òfin mi,

Tí wọn ò sì pa àwọn àṣẹ mi mọ́,

 32 Nígbà náà, màá fi ọ̀pá nà wọ́n nítorí àìgbọ́ràn* wọn,+

Màá sì fi ẹgba nà wọ́n nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wọn.

33 Àmọ́ mi ò ní mú ìfẹ́ mi tí kì í yẹ̀ kúrò lórí rẹ̀ láé,+

Mi ò sì ní ṣàì mú ìlérí mi ṣẹ.*

34 Mi ò ní da májẹ̀mú mi,+

Mi ò sì ní yí ohun tí ẹnu mi ti sọ pa dà.+

35 Mo ti búra nínú ìjẹ́mímọ́ mi, lẹ́ẹ̀kan láìtún ṣe é mọ́;

Mi ò ní parọ́ fún Dáfídì.+

36 Àwọn ọmọ* rẹ̀ yóò wà títí láé;+

Ìtẹ́ rẹ̀ yóò wà títí lọ bí oòrùn níwájú mi.+

37 Yóò fìdí múlẹ̀ títí láé bí òṣùpá

Bí ẹlẹ́rìí tó ṣeé gbára lé ní ojú ọ̀run.” (Sélà)

38 Àmọ́ ìwọ fúnra rẹ ti tá a nù, o sì ti kọ̀ ọ́ sílẹ̀;+

O ti bínú gidigidi sí ẹni àmì òróró rẹ.

39 O ti pa májẹ̀mú rẹ tì, èyí tí o bá ìránṣẹ́ rẹ dá;

O ti sọ adé* rẹ̀ di aláìmọ́ bí o ṣe jù ú sílẹ̀.

 40 O ti wó gbogbo àwọn ògiri* olókùúta rẹ̀ lulẹ̀;

O ti sọ àwọn ibi olódi rẹ̀ di àwókù.

41 Gbogbo àwọn tó kọjá ló kó ẹrù rẹ̀ lọ;

Ó ti di ẹni ẹ̀gàn lọ́dọ̀ àwọn aládùúgbò rẹ̀.+

42 O ti mú kí àwọn elénìní rẹ̀ borí;*+

O ti mú kí gbogbo àwọn ọ̀tá rẹ̀ máa yọ̀.

43 Bákan náà, o ò jẹ́ kí idà rẹ̀ wúlò,

O ò sì jẹ́ kó rọ́wọ́ mú lójú ogun.

44 O ti mú kí ọlá ńlá rẹ̀ pa rẹ́,

O sì ti wó ìtẹ́ rẹ̀ mọ́lẹ̀.

45 O ti gé ìgbà ọ̀dọ́ rẹ̀ kúrú;

O ti fi ìtìjú wọ̀ ọ́ láṣọ. (Sélà)

 46 Jèhófà, ìgbà wo lo máa fi ara rẹ pa mọ́ dà? Ṣé títí láé ni?+

Ṣé ìbínú ńlá rẹ yóò máa jó lọ bí iná ni?

47 Rántí bí ọjọ́ ayé mi ṣe kúrú tó!+

Ṣé lásán lo dá gbogbo èèyàn ni?

48 Ta ló wà láàyè tí kò ní kú?+

Ṣé ó lè gba ara* rẹ̀ lọ́wọ́ agbára Isà Òkú ni?* (Sélà)

49 Jèhófà, ibo ni ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ ti ìgbà àtijọ́ wà,

Èyí tí o búra nípa rẹ̀ fún Dáfídì nínú òtítọ́ rẹ?+

50 Jèhófà, rántí ẹ̀gàn tí wọ́n kó bá ìránṣẹ́ rẹ;

Bí mo ṣe fara da ẹ̀gàn gbogbo èèyàn;*

51 Jèhófà, rántí bí àwọn ọ̀tá rẹ ṣé ń sọ̀kò ọ̀rọ̀;

Bí wọ́n ṣe pẹ̀gàn gbogbo ìṣísẹ̀ ẹni àmì òróró rẹ.

52 Ìyìn ni fún Jèhófà títí láé. Àmín àti Àmín.+

ÌWÉ KẸRIN

(Sáàmù 90-106)

Àdúrà Mósè, èèyàn Ọlọ́run tòótọ́.+

90 Jèhófà, ìwọ ni ibùgbé*+ wa láti ìran dé ìran.

 2 Kí a tó bí àwọn òkè

Tàbí kí o tó dá ayé àti ilẹ̀ tó ń méso jáde,*+

Láti ayérayé dé ayérayé,* ìwọ ni Ọlọ́run.+

 3 O mú kí ẹni kíkú pa dà sínú erùpẹ̀;

O sọ pé: “Ẹ pa dà, ẹ̀yin ọmọ èèyàn.”+

 4 Nítorí bí ẹgbẹ̀rún ọdún bá kọjá, á dà bí àná lójú rẹ,+

Bí ìṣọ́ kan ní òru.

 5 O gbá wọn lọ;+ wọ́n dà bí oorun lásán;

Ní àárọ̀, wọ́n dà bíi koríko tó yọ.+

 6 Ní àárọ̀, ó yọ ìtànná, ó sì dọ̀tun,

Àmọ́ ní ìrọ̀lẹ́, ó rọ, ó sì gbẹ dà nù.+

 7 Nítorí pé ìbínú rẹ ti pa wá run,+

Ìrunú rẹ sì ti da jìnnìjìnnì bò wá.

 8 O gbé àwọn àṣìṣe wa sí iwájú rẹ;*+

Ìmọ́lẹ̀ ojú rẹ tú àwọn àṣírí wa.+

 9 Àwọn ọjọ́ ayé wa* ń dín kù nítorí ìbínú ńlá rẹ;

Àwọn ọdún wa ń lọ sí òpin bí ọ̀rọ̀ wúyẹ́wúyẹ́.*

10 Àádọ́rin (70) ọdún ni gígùn ọjọ́ ayé wa,

Tàbí kó jẹ́ ọgọ́rin (80) ọdún+ tí èèyàn bá lókun tó ṣàrà ọ̀tọ̀.*

Síbẹ̀, wàhálà àti ìbànújẹ́ ló kún inú wọn;

Wọ́n á kọjá lọ kíákíá, a ó sì fò lọ.+

11 Ta ló lè fòye mọ bí ìbínú rẹ ṣe le tó?

Bí ìbínú ńlá rẹ ṣe pọ̀ ni ẹ̀rù tó yẹ ọ́ ṣe pọ̀.+

12 Kọ́ wa bí a ó ṣe máa ka àwọn ọjọ́ wa+

Ká lè ní ọkàn ọgbọ́n.

13 Pa dà, Jèhófà!+ Ìgbà wo ni èyí máa dópin?+

Ṣàánú àwọn ìránṣẹ́ rẹ.+

14 Fi ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀+ tẹ́ wa lọ́rùn ní àárọ̀,

Ká lè máa kígbe ayọ̀, kí inú wa sì máa dùn+ ní gbogbo ọjọ́ ayé wa.

15 Jẹ́ kí ọjọ́ tí inú wa yóò fi máa dùn pọ̀ bí iye ọjọ́ tí o fi fìyà jẹ wá,+

Kí ó sì pọ̀ bí àwọn ọdún tí àjálù fi bá wa.+

16 Kí àwọn ìránṣẹ́ rẹ rí iṣẹ́ rẹ,

Kí àwọn ọmọ wọn sì rí ọlá ńlá rẹ.+

17 Kí ojú rere Jèhófà Ọlọ́run wa wà lára wa;

Mú kí iṣẹ́ ọwọ́ wa yọrí sí rere.*

Bẹ́ẹ̀ ni, mú kí iṣẹ́ ọwọ́ wa yọrí sí rere.*+

91 Ẹni tó bá ń gbé ibi ìkọ̀kọ̀ Ẹni Gíga Jù Lọ+

Yóò máa gbé lábẹ́ òjìji Olódùmarè.+

 2 Màá sọ fún Jèhófà pé: “Ìwọ ni ibi ààbò mi àti odi ààbò mi,+

Ọlọ́run mi tí mo gbẹ́kẹ̀ lé.”+

 3 Nítorí yóò gbà ọ́ lọ́wọ́ pańpẹ́ pẹyẹpẹyẹ,

Lọ́wọ́ àjàkálẹ̀ àrùn tó ń pani run.

 4 Yóò fi àwọn ìyẹ́ tó fi ń fò bò ọ́,*

Wàá sì fi abẹ́ ìyẹ́ apá rẹ̀ ṣe ibi ààbò.+

Òtítọ́ rẹ̀+ yóò jẹ́ apata+ ńlá àti odi* ààbò.

 5 O ò ní bẹ̀rù àwọn ohun tó ń kó jìnnìjìnnì báni ní òru+

Tàbí ọfà tó ń fò ní ọ̀sán+

 6 Tàbí àjàkálẹ̀ àrùn tó ń yọ́ kẹ́lẹ́ nínú òkùnkùn

Tàbí ìparun tó ń ṣọṣẹ́ ní ọ̀sán gangan.

 7 Ẹgbẹ̀rún yóò ṣubú ní ẹ̀gbẹ́ rẹ

Àti ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ,

Àmọ́ kò ní sún mọ́ ọ.+

 8 Ojú rẹ nìkan ni wàá fi rí i

Bí o ṣe ń wo ìyà* àwọn ẹni burúkú.

 9 Nítorí o sọ pé: “Jèhófà ni ibi ààbò mi,”

O ti fi Ẹni Gíga Jù Lọ ṣe ibùgbé* rẹ;+

10 Àjálù kankan kò ní bá ọ,+

Àjàkálẹ̀ àrùn kankan kò sì ní sún mọ́ àgọ́ rẹ.

11 Torí ó máa pàṣẹ fún àwọn áńgẹ́lì rẹ̀ nítorí rẹ,+

Láti máa ṣọ́ ọ ní gbogbo ọ̀nà rẹ.+

12 Wọ́n á fi ọwọ́ wọn gbé ọ,+

Kí o má bàa fi ẹsẹ̀ rẹ gbá òkúta.+

13 Wàá rìn kọjá lórí ọmọ kìnnìún àti ṣèbé;

Wàá tẹ kìnnìún onígọ̀gọ̀* àti ejò ńlá mọ́lẹ̀.+

14 Ọlọ́run sọ pé: “Nítorí ó nífẹ̀ẹ́ mi,* màá gbà á sílẹ̀.+

Màá dáàbò bò ó torí pé ó mọ* orúkọ mi.+

15 Yóò ké pè mí, màá sì dá a lóhùn.+

Màá dúró tì í nígbà wàhálà.+

Màá gbà á sílẹ̀, màá sì ṣe é lógo.

16 Màá fi ẹ̀mí gígùn tẹ́ ẹ lọ́rùn,+

Màá sì jẹ́ kó rí àwọn iṣẹ́ ìgbàlà mi.”*+

Orin atunilára. Orin ọjọ́ Sábáàtì.

92 Ó dára láti máa fi ọpẹ́ fún Jèhófà+

Àti láti máa fi orin yin* orúkọ rẹ, ìwọ Ẹni Gíga Jù Lọ,

 2 Láti máa kéde ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀+ ní àárọ̀

Àti òtítọ́ rẹ ní òru,

 3 Pẹ̀lú ohun ìkọrin olókùn tín-ín-rín mẹ́wàá àti gòjé,

Nípasẹ̀ háàpù tó ń dún dáadáa.+

 4 Jèhófà, ò ń mú inú mi dùn, nítorí àwọn ohun tí ò ń ṣe;

Mò ń kígbe ayọ̀ nítorí àwọn iṣẹ́ ọwọ́ rẹ.

 5 Àwọn iṣẹ́ rẹ mà tóbi o, Jèhófà!+

Èrò rẹ jinlẹ̀ gidigidi!+

 6 Kò sí aláìnírònú tó lè mọ̀ wọ́n;

Kò sì sí òmùgọ̀ tó lè lóye èyí:+

 7 Nígbà tí àwọn ẹni burúkú bá rú jáde bíi koríko*

Tí gbogbo àwọn aṣebi sì gbilẹ̀,

Kí wọ́n lè pa run títí láé ni.+

 8 Àmọ́, ẹni gíga ni ọ́ títí láé, Jèhófà.

 9 Wo ìṣubú àwọn ọ̀tá rẹ, Jèhófà,

Wo bí àwọn ọ̀tá rẹ ṣe máa ṣègbé;

Gbogbo àwọn aṣebi yóò tú ká.+

10 Àmọ́ wàá mú kí agbára mi pọ̀ sí i* bíi ti akọ màlúù igbó;

Màá fi òróró dáradára para.+

11 Ojú mi á rí ìṣubú àwọn ọ̀tá mi;+

Etí mi á gbọ́ nípa ìṣubú àwọn aṣebi tó ń bá mi jà.

12 Àmọ́ olódodo máa gbilẹ̀ bí igi ọ̀pẹ

Wọ́n á sì tóbi bí igi kédárì ní Lẹ́bánónì.+

13 Ilé Jèhófà ni a gbìn wọ́n sí;

Wọ́n ń gbilẹ̀ ní àwọn àgbàlá Ọlọ́run wa.+

14 Kódà nígbà arúgbó* wọn, wọ́n á máa lókun;+

Wọ́n á ṣì máa ta kébé,* ara wọn á sì máa dán,+

15 Láti máa kéde pé adúróṣinṣin ni Jèhófà.

Òun ni Àpáta+ mi, ẹni tí kò sí àìṣòdodo nínú rẹ̀.

93 Jèhófà ti di Ọba!+

Ó gbé ọlá ńlá wọ̀ bí aṣọ;

Jèhófà gbé agbára wọ̀;

Ó fi di ara rẹ̀ bí àmùrè.

Ayé* fìdí múlẹ̀ gbọn-in;

Kò ṣeé ṣí nípò.*

 2 Tipẹ́tipẹ́ ni ìtẹ́ rẹ ti fìdí múlẹ̀ gbọn-in;+

O ti wà láti ayébáyé.+

 3 Àwọn odò ru sókè, Jèhófà,

Àwọn odò ru sókè, wọ́n sì pariwo;

Àwọn odò ń ru sókè, wọ́n ń ru gùdù.

 4 Jèhófà jẹ́ ọlọ́lá ńlá ní ibi gíga,+

Lórí ìró omi púpọ̀,

Agbára rẹ̀ ju ti ìgbì òkun tó ń ru gùdù lọ.+

 5 Àwọn ìránnilétí rẹ ṣeé gbẹ́kẹ̀ lé pátápátá.+

Jèhófà, ìjẹ́mímọ́ ni ọ̀ṣọ́* ilé rẹ+ títí láé.

94 Jèhófà, Ọlọ́run ẹ̀san,+

Ìwọ Ọlọ́run ẹ̀san, máa tàn yanran!

 2 Dìde, ìwọ Onídàájọ́ ayé.+

San àwọn agbéraga ní ẹ̀san tó yẹ wọ́n.+

 3 Ìgbà wo, Jèhófà,

Ìgbà wo ni àwọn ẹni burúkú ò ní yọ̀ mọ́?+

 4 Wọ́n ń sọ̀rọ̀ yàùyàù, wọ́n sì ń sọ̀rọ̀ ìgbéraga;

Gbogbo àwọn aṣebi ń fọ́nnu nípa ara wọn.

 5 Jèhófà, wọ́n tẹ àwọn èèyàn rẹ mọ́lẹ̀,+

Wọ́n sì ń fìyà jẹ ogún rẹ.

 6 Wọ́n pa opó àti àjèjì,

Wọ́n sì pa àwọn ọmọ aláìníbaba.

 7 Wọ́n ń sọ pé: “Jáà kò rí i;+

Ọlọ́run Jékọ́bù kò kíyè sí i.”+

 8 Ẹ jẹ́ kó yé yín, ẹ̀yin aláìnírònú;

Ẹ̀yin òmùgọ̀, ìgbà wo lẹ máa ní ìjìnlẹ̀ òye?+

 9 Ẹni tó dá* etí, ṣé kò lè gbọ́ràn ni?

Ẹni tó dá ojú, ṣé kò lè ríran ni?+

10 Ẹni tó ń tọ́ àwọn orílẹ̀-èdè sọ́nà, ṣé kò lè báni wí ni?+

Òun ló ń fún àwọn èèyàn ní ìmọ̀!+

11 Jèhófà mọ èrò àwọn èèyàn,

Ó mọ̀ pé èémí lásán ni wọ́n.+

12 Aláyọ̀ ni ẹni tí o tọ́ sọ́nà, Jáà,+

Ẹni tí o kọ́ ní òfin rẹ,+

13 Kí o lè fún un ní ìsinmi ní ọjọ́ àjálù,

Títí a ó fi gbẹ́ kòtò fún ẹni burúkú.+

14 Nítorí Jèhófà ò ní pa àwọn èèyàn rẹ̀ tì,+

Kò sì ní fi ogún rẹ̀ sílẹ̀.+

15 A ó tún pa dà máa ṣe ìdájọ́ lọ́nà òdodo,

Gbogbo àwọn tí ọkàn wọn dúró ṣinṣin yóò sì máa tẹ̀ lé e.

16 Ta ló máa bá mi dìde sí ẹni burúkú?

Ta ló máa gbèjà mi níwájú àwọn aṣebi?

17 Tí kì í bá ṣe ti Jèhófà tó ràn mí lọ́wọ́,

Ká tó ṣẹ́jú pẹ́ ni ǹ bá* ti ṣègbé.*+

18 Nígbà tí mo sọ pé: “Ẹsẹ̀ mi ń yọ̀,”

Jèhófà, ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ ló ń gbé mi ró.+

19 Nígbà tí àníyàn* bò mí mọ́lẹ̀,*

O tù mí nínú, o sì tù mí lára.*+

20 Ṣé ìtẹ́* ìwà ìbàjẹ́ lè ní nǹkan ṣe pẹ̀lú rẹ

Nígbà tó ń fi òfin bojú láti* dáná ìjàngbọ̀n?+

21 Wọ́n ń ṣe àtakò tó lágbára sí olódodo,*+

Wọ́n sì ń dájọ́ ikú fún aláìṣẹ̀.*+

22 Àmọ́ Jèhófà máa di ibi ààbò* fún mi,

Ọlọ́run mi ni àpáta ààbò mi.+

23 Yóò mú kí iṣẹ́ ibi wọn dà lé wọn lórí.+

Yóò fi iṣẹ́ ibi wọn pa wọ́n run.*

Jèhófà Ọlọ́run wa yóò pa wọ́n run.*+

95 Ẹ wá, ẹ jẹ́ ká kígbe ayọ̀ sí Jèhófà!

Ẹ jẹ́ ká kígbe ìṣẹ́gun sí Àpáta ìgbàlà wa.+

 2 Ẹ jẹ́ ká wá sí iwájú* rẹ̀ pẹ̀lú ọpẹ́;+

Ẹ jẹ́ ká kọrin, ká sì kígbe ìṣẹ́gun sí i.

 3 Nítorí pé Ọlọ́run ńlá ni Jèhófà,

Ọba ńlá lórí gbogbo àwọn ọlọ́run yòókù.+

 4 Ọwọ́ rẹ̀ ni ọ̀gbun ayé wà;

Àwọn téńté orí òkè jẹ́ tirẹ̀.+

 5 Òkun jẹ́ tirẹ̀, òun ló dá a,+

Ọwọ́ rẹ̀ ló sì dá ilẹ̀ gbígbẹ.+

 6 Ẹ wá, ẹ jẹ́ ká jọ́sìn, ká sì forí balẹ̀;

Ẹ jẹ́ ká kúnlẹ̀ níwájú Jèhófà Ẹni tó dá wa.+

 7 Nítorí òun ni Ọlọ́run wa,

Àwa sì ni èèyàn ibi ìjẹko rẹ̀,

Àgùntàn tó wà lábẹ́ àbójútó rẹ̀.*+

Lónìí, tí ẹ bá fetí sí ohùn rẹ̀,+

 8 Ẹ má ṣe mú kí ọkàn yín le bí ẹ ṣe ṣe ní Mẹ́ríbà,*+

Bíi ti ọjọ́ Másà* ní aginjù,+

 9 Nígbà tí àwọn baba ńlá yín dán mi wò;+

Wọ́n pè mí níjà, bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ti rí àwọn iṣẹ́ mi.+

10 Ogójì (40) ọdún ni mo fi kórìíra ìran yẹn, mo sì sọ pé:

“Àwọn èèyàn tó máa ń ṣìnà nínú ọkàn wọn ni wọ́n;

Wọn ò tíì mọ àwọn ọ̀nà mi.”

11 Torí náà, mo búra nínú ìbínú mi pé:

“Wọn ò ní wọnú ìsinmi mi.”+

96 Ẹ kọ orin tuntun sí Jèhófà.+

Ẹ kọrin sí Jèhófà, gbogbo ayé!+

 2 Ẹ kọrin sí Jèhófà; ẹ yin orúkọ rẹ̀.

Ẹ máa kéde ìhìn rere ìgbàlà rẹ̀ láti ọjọ́ dé ọjọ́.+

 3 Ẹ máa kéde ògo rẹ̀ láàárín àwọn orílẹ̀-èdè,

Àwọn iṣẹ́ àgbàyanu rẹ̀ láàárín gbogbo àwọn èèyàn.+

 4 Jèhófà tóbi, òun sì ni ìyìn yẹ jù lọ.

Ó yẹ lẹ́ni tí à ń bẹ̀rù ju gbogbo ọlọ́run yòókù lọ.

 5 Gbogbo ọlọ́run àwọn èèyàn jẹ́ ọlọ́run asán,+

Àmọ́ Jèhófà ló dá ọ̀run.+

 6 Ògo àti ọlá ńlá* wà pẹ̀lú rẹ̀;+

Agbára àti ẹwà wà ní ibi mímọ́ rẹ̀.+

 7 Ẹ fún Jèhófà ní ohun tí ó tọ́ sí i, ẹ̀yin ìdílé gbogbo ayé,

Ẹ fún Jèhófà ní ohun tí ó tọ́ sí i nítorí ògo àti agbára rẹ̀.+

 8 Ẹ fún Jèhófà ní ògo tí ó yẹ orúkọ rẹ̀;+

Ẹ mú ẹ̀bùn dání wá sínú àwọn àgbàlá rẹ̀.

 9 Ẹ forí balẹ̀ fún* Jèhófà nínú aṣọ ọ̀ṣọ́ mímọ́;*

Kí jìnnìjìnnì bá yín níwájú rẹ̀, gbogbo ayé!

10 Ẹ kéde láàárín àwọn orílẹ̀-èdè pé: “Jèhófà ti di Ọba!+

Ayé* fìdí múlẹ̀ gbọn-in gbọn-in, kò ṣeé ṣí nípò.*

Òun yóò dá ẹjọ́ àwọn èèyàn* lọ́nà tí ó tọ́.”+

11 Kí ọ̀run yọ̀, kí inú ayé sì dùn;

Kí òkun àti gbogbo ohun tó wà nínú rẹ̀ dún bí ààrá;+

12 Kí àwọn pápá àti gbogbo ohun tó wà lórí wọn máa dunnú.+

Ní àkókò kan náà, kí gbogbo igi igbó kígbe ayọ̀+

13 Níwájú Jèhófà, nítorí ó ń bọ̀,*

Ó ń bọ̀ wá ṣe ìdájọ́ ayé.

Yóò fi òdodo ṣe ìdájọ́ ilẹ̀ ayé tí à ń gbé,*+

Yóò sì fi òtítọ́ ṣe ìdájọ́ àwọn èèyàn.+

97 Jèhófà ti di Ọba!+

Kí inú ayé máa dùn.+

Kí ọ̀pọ̀ erékùṣù máa yọ̀.+

 2 Ìkùukùu àti ìṣúdùdù tó kàmàmà yí i ká;+

Òtítọ́ àti ìdájọ́ òdodo ni ìpìlẹ̀ ìtẹ́ rẹ̀.+

 3 Iná ń lọ níwájú rẹ̀,+

Ó sì ń jó àwọn ọ̀tá rẹ̀ run yí ká.+

 4 Mànàmáná rẹ̀ mú kí ilẹ̀ mọ́lẹ̀ kedere;

Ayé rí i, ó sì ń gbọ̀n.+

 5 Àwọn òkè yọ́ bí ìda níwájú Jèhófà,+

Níwájú Olúwa gbogbo ayé.

 6 Ọ̀run ń kéde òdodo rẹ̀,

Gbogbo èèyàn sì ń rí ògo rẹ̀.+

 7 Kí ojú ti gbogbo àwọn tó ń sin ère gbígbẹ́,+

Àwọn tó ń fi àwọn ọlọ́run asán+ wọn yangàn.

Ẹ forí balẹ̀ fún un,* gbogbo ẹ̀yin ọlọ́run.+

 8 Síónì gbọ́, ó sì ń yọ̀;+

Inú àwọn ìlú* Júdà ń dùn

Nítorí àwọn ìdájọ́ rẹ, Jèhófà.+

 9 Nítorí pé, ìwọ Jèhófà ni Ẹni Gíga Jù Lọ lórí gbogbo ayé;

O ga fíìfíì ju gbogbo àwọn ọlọ́run yòókù.+

10 Ẹ̀yin tí ẹ nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, ẹ kórìíra ohun tó burú.+

Ó ń ṣọ́ ẹ̀mí* àwọn ẹni ìdúróṣinṣin rẹ̀;+

Ó ń gbà wọ́n sílẹ̀ lọ́wọ́* àwọn ẹni burúkú.+

11 Ìmọ́lẹ̀ ti tàn fún olódodo,+

Ayọ̀ sì kún inú àwọn tí ọkàn wọn dúró ṣinṣin.

12 Ẹ máa yọ̀ nínú Jèhófà, ẹ̀yin olódodo,

Ẹ sì máa fi ọpẹ́ fún orúkọ mímọ́* rẹ̀.

Orin.

98 Ẹ kọ orin tuntun sí Jèhófà,+

Nítorí ó ti ṣe àwọn ohun àgbàyanu.+

Ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀, àní apá mímọ́ rẹ̀, ti mú ìgbàlà wá.*+

 2 Jèhófà ti jẹ́ kí á mọ ìgbàlà rẹ̀;+

Ó ti mú kí àwọn orílẹ̀-èdè rí òdodo rẹ̀.+

 3 Ó rántí ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ àti òtítọ́ rẹ̀ sí ilé Ísírẹ́lì.+

Gbogbo ayé ti rí ìgbàlà* Ọlọ́run wa.+

 4 Ẹ kígbe ìṣẹ́gun sí Jèhófà, gbogbo ayé.

Ẹ túra ká, ẹ kígbe ayọ̀, kí ẹ sì kọ orin ìyìn.*+

 5 Ẹ fi háàpù kọ orin ìyìn* sí Jèhófà,

Àní háàpù àti orin tó dùn.

 6 Pẹ̀lú kàkàkí àti ìró ìwo,+

Ẹ kígbe ìṣẹ́gun níwájú Ọba náà, Jèhófà.

 7 Kí òkun àti gbogbo ohun tó wà nínú rẹ̀ dún bí ààrá,

Ayé* àti àwọn tó ń gbé inú rẹ̀.

 8 Kí àwọn odò pàtẹ́wọ́;

Kí àwọn òkè kígbe ayọ̀ pa pọ̀+

 9 Níwájú Jèhófà, nítorí ó ń bọ̀ wá* ṣe ìdájọ́ ayé.

Yóò fi òdodo ṣe ìdájọ́ ilẹ̀ ayé tí à ń gbé,*+

Yóò sì dá ẹjọ́ àwọn èèyàn lọ́nà tí ó tọ́.+

99 Jèhófà ti di Ọba.+ Kí jìnnìjìnnì bá àwọn èèyàn.

Ó gúnwà lórí* àwọn kérúbù.+ Kí ayé mì tìtì.

 2 Jèhófà tóbi ní Síónì,

Ó sì ga ju gbogbo èèyàn lọ.+

 3 Kí wọ́n yin orúkọ ńlá rẹ,+

Torí ó ń bani lẹ́rù, ó sì jẹ́ mímọ́.

 4 Ọba alágbára ńlá tó nífẹ̀ẹ́ ìdájọ́ òdodo ni.+

O ti fìdí ohun tí ó tọ́ múlẹ̀ ṣinṣin.

O ti mú kí ìdájọ́ òdodo+ àti òtítọ́ wà ní Jékọ́bù.

 5 Ẹ gbé Jèhófà Ọlọ́run wa ga,+ kí ẹ sì forí balẹ̀* níbi àpótí ìtìsẹ̀ rẹ̀;+

Ẹni mímọ́ ni.+

 6 Mósè àti Áárónì wà lára àwọn àlùfáà rẹ̀,+

Sámúẹ́lì sì wà lára àwọn tó ń ké pe orúkọ rẹ̀.+

Wọ́n ń pe Jèhófà,

Ó sì ń dá wọn lóhùn.+

 7 Ó ń bá wọn sọ̀rọ̀ látinú ọwọ̀n ìkùukùu.*+

Wọ́n pa àwọn ìránnilétí rẹ̀ àti àṣẹ tó fún wọn mọ́.+

 8 Jèhófà Ọlọ́run wa, o dá wọn lóhùn.+

Ìwọ ni Ọlọ́run tó ń dárí jì wọ́n,+

Àmọ́ o fìyà jẹ wọ́n* nítorí ẹ̀ṣẹ̀ tí wọ́n dá.+

 9 Ẹ gbé Jèhófà Ọlọ́run wa ga,+

Kí ẹ sì forí balẹ̀* níwájú òkè mímọ́ rẹ̀.+

Nítorí Jèhófà Ọlọ́run wa jẹ́ mímọ́.+

Orin ọpẹ́.

100 Ẹ kígbe ìṣẹ́gun sí Jèhófà, gbogbo ayé.+

 2 Ẹ fi ayọ̀ sin Jèhófà.+

Ẹ fi igbe ayọ̀ wá síwájú rẹ̀.

 3 Kí ẹ mọ̀* pé Jèhófà ni Ọlọ́run.+

Òun ló dá wa, tirẹ̀ la sì jẹ́.*+

Àwa ni èèyàn rẹ̀ àti àgùntàn ibi ìjẹko rẹ̀.+

 4 Ẹ wọlé sínú àwọn ẹnubodè rẹ̀ pẹ̀lú ọpẹ́,+

Sínú àwọn àgbàlá rẹ̀ pẹ̀lú ìyìn.+

Ẹ fi ọpẹ́ fún un; ẹ yin orúkọ rẹ̀.+

 5 Nítorí Jèhófà jẹ́ ẹni rere;+

Ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí láé,

Òtítọ́ rẹ̀ sì wà láti ìran dé ìran.+

Ti Dáfídì. Orin.

101 Màá kọrin nípa ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ àti ìdájọ́ òdodo.

Jèhófà, ìwọ ni màá kọ orin ìyìn sí.*

 2 Màá hu ìwà ọgbọ́n àti ìwà àìlábààwọ́n.*

Ìgbà wo lo máa wá bá mi?

Màá fi òtítọ́ ọkàn+ rìn nínú ilé mi.

 3 Mi ò ní gbé ohun tí kò ní láárí* sí iwájú mi.

Mo kórìíra iṣẹ́ àwọn tó ń yà kúrò nínú ohun tí ó tọ́;+

Mi ò ní bá wọn da nǹkan kan pọ̀.*

 4 Ọkàn ẹ̀tàn jìnnà sí mi;

Mi ò ní gba* ohun búburú kankan.

 5 Ẹnikẹ́ni tó bá ń ba ọmọnìkejì rẹ̀ jẹ́ ní ìkọ̀kọ̀,+

Màá pa á lẹ́nu mọ́.*

Ẹnikẹ́ni tó bá ní ojú ìgbéraga àti ọkàn gíga,

Mi ò ní gbà á láyè.

 6 Màá bojú wo àwọn olóòótọ́ ayé,

Kí wọ́n lè máa bá mi gbé.

Ẹni tó ń rìn láìní àbààwọ́n* yóò máa ṣe ìránṣẹ́ fún mi.

 7 Kò sí ẹlẹ́tàn kankan tó máa gbé inú ilé mi,

Kò sì sí òpùrọ́ kankan tó máa dúró níwájú* mi.

 8 Ní àràárọ̀, màá pa gbogbo àwọn ẹni burúkú ayé lẹ́nu mọ́,*

Láti mú gbogbo àwọn aṣebi kúrò ní ìlú Jèhófà.+

Àdúrà ẹni tí ìnilára bá nígbà tí nǹkan tojú sú u,* tó sì ń sọ ẹ̀dùn ọkàn rẹ̀ níwájú Jèhófà.+

102 Jèhófà, gbọ́ àdúrà mi;+

Jẹ́ kí igbe mi fún ìrànlọ́wọ́ dé ọ̀dọ̀ rẹ.+

 2 Má fi ojú rẹ pa mọ́ fún mi nígbà tí mo wà nínú wàhálà.+

Tẹ́tí sí mi;*

Tètè dá mi lóhùn nígbà tí mo bá pè ọ́.+

 3 Nítorí àwọn ọjọ́ mi ń pa rẹ́ lọ bí èéfín,

Àwọn egungun mi sì ti di dúdú bí ibi ìdáná.+

 4 Ọkàn mi dà bíi koríko tí a gé, tó sì ti rọ,+

Nítorí mi ò rántí jẹ oúnjẹ mi.

 5 Nítorí bí mo ṣe ń kérora gidigidi,+

Egungun mi ti lẹ̀ mọ́ ẹran ara mi.+

 6 Mo dà bí ẹyẹ òfú tó wà ní aginjù;

Mo dà bí òwìwí kékeré tó wà láàárín àwókù.

 7 Mi ò rí oorun sùn;*

Mo dà bí ẹyẹ tó dá wà lórí òrùlé.+

 8 Àwọn ọ̀tá mi ń pẹ̀gàn mi láti àárọ̀ ṣúlẹ̀.+

Àwọn tó ń fi mí ṣẹ̀sín* ń lo orúkọ mi tí wọ́n bá fẹ́ gégùn-ún.

 9 Eérú ni mo fi ń ṣe oúnjẹ jẹ,+

Omijé sì ti dà pọ̀ mọ́ ohun tí mò ń mu,+

10 Nítorí ìbínú rẹ àti ìrunú rẹ,

O gbé mi sókè kí o lè jù mí sí ẹ̀gbẹ́ kan.

11 Àwọn ọjọ́ mi dà bí òjìji tó ń pa rẹ́ lọ,*+

Mo sì ń rọ bíi koríko.+

12 Àmọ́, Jèhófà, o wà títí láé,+

Òkìkí rẹ yóò sì máa kàn* láti ìran dé ìran.+

13 Ó dájú pé wàá dìde, wàá sì ṣàánú Síónì,+

Torí àkókò ti tó láti ṣe ojú rere sí i;+

Àkókò tí a dá ti pé.+

14 Nítorí àwọn ìránṣẹ́ rẹ fẹ́ràn àwọn òkúta rẹ̀,+

Kódà, wọ́n nífẹ̀ẹ́ erùpẹ̀ rẹ̀.+

15 Àwọn orílẹ̀-èdè yóò máa bẹ̀rù orúkọ Jèhófà,

Gbogbo ọba ayé yóò sì máa bẹ̀rù ògo rẹ.+

16 Jèhófà máa tún Síónì kọ́;+

Á fara hàn nínú ògo rẹ̀.+

17 Á fetí sí àdúrà àwọn òtòṣì,+

Kò sì ní kó àdúrà wọn dà nù.+

18 A kọ èyí sílẹ̀ torí ìran tó ń bọ̀,+

Kí àwọn èèyàn tí a ó bí* lè yin Jáà.

19 Ó ń bojú wolẹ̀ láti ibi gíga rẹ̀ mímọ́,+

Láti ọ̀run, Jèhófà ń wo ayé,

20 Kí ó lè gbọ́ bí ẹlẹ́wọ̀n ṣe ń kérora,+

Kí ó lè dá àwọn tí wọ́n ti dájọ́ ikú fún sílẹ̀,+

21 Ká lè kéde orúkọ Jèhófà ní Síónì+

Àti ìyìn rẹ̀ ní Jerúsálẹ́mù,

22 Nígbà tí àwọn èèyàn àti àwọn ìjọba

Bá kóra jọ láti sin Jèhófà.+

23 Ó gba agbára mi láìtọ́jọ́;

Ó gé ọjọ́ ayé mi kúrú.

24 Mo sọ pé: “Ìwọ Ọlọ́run mi,

Má ṣe dá ẹ̀mí mi légbodò,*

Ìwọ tí àwọn ọdún rẹ lọ láti ìran dé ìran.+

25 Tipẹ́tipẹ́ lo ti fi ìpìlẹ̀ ayé sọlẹ̀,

Ọ̀run sì jẹ́ iṣẹ́ ọwọ́ rẹ.+

26 Wọ́n á ṣègbé, àmọ́ ìwọ á máa wà nìṣó;

Gbogbo wọn á gbó bí aṣọ.

Wàá pààrọ̀ wọn bí aṣọ, wọn ò sì ní sí mọ́.

27 Àmọ́ ìwọ kò yí pa dà, àwọn ọdún rẹ kò sì ní dópin láé.+

28 Ọmọ àwọn ìránṣẹ́ rẹ yóò máa wà láìséwu,

A ó sì fìdí àtọmọdọ́mọ wọn múlẹ̀ gbọn-in níwájú rẹ.”+

Ti Dáfídì.

103 Jẹ́ kí n* yin Jèhófà;

Kí gbogbo ohun tó wà nínú mi yin orúkọ mímọ́ rẹ̀.

 2 Jẹ́ kí n* yin Jèhófà;

Kí n má gbàgbé gbogbo ohun tó ti ṣe láé.+

 3 Ó ń dárí gbogbo àṣìṣe mi jì mí,+

Ó sì ń wo gbogbo àìsàn mi sàn;+

 4 Ó gba ẹ̀mí mi pa dà látinú kòtò,*+

Ó sì fi ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ àti àánú dé mi ládé,+

 5 Ó ń fi ohun rere tẹ́ mi lọ́rùn+ ní gbogbo ọjọ́ ayé mi,

Kí agbára* mi lè di ọ̀tun bíi ti ẹyẹ idì.+

 6 Jèhófà ń fi òtítọ́ àti ìdájọ́ òdodo hùwà+

Sí gbogbo àwọn tí à ń ni lára.+

 7 Ó jẹ́ kí Mósè mọ àwọn ọ̀nà rẹ̀,+

Ó sì jẹ́ kí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì mọ àwọn iṣẹ́ rẹ̀.+

 8 Aláàánú ni Jèhófà, ó sì ń gba tẹni rò,*+

Kì í tètè bínú, ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀* sì pọ̀ gidigidi.+

 9 Kì í fìgbà gbogbo wá àṣìṣe,+

Kì í sì í bínú títí lọ.+

10 Kò fi àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa hùwà sí wa,+

Kò sì fi ìyà tó yẹ àṣìṣe wa jẹ wá.+

11 Nítorí bí ọ̀run ṣe ga ju ayé,

Bẹ́ẹ̀ ni ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ tó ní sí àwọn tó bẹ̀rù rẹ̀ ṣe ga.+

12 Bí yíyọ oòrùn ṣe jìnnà sí wíwọ̀ oòrùn,

Bẹ́ẹ̀ ni ó ṣe mú àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa jìnnà sí wa.+

13 Bí bàbá ṣe ń ṣàánú àwọn ọmọ rẹ̀,

Bẹ́ẹ̀ ni Jèhófà ń ṣàánú àwọn tó bẹ̀rù rẹ̀.+

14 Nítorí ó mọ ẹ̀dá wa,+

Ó rántí pé erùpẹ̀ ni wá.+

15 Ní ti ẹni kíkú, àwọn ọjọ́ rẹ̀ dà bíi ti koríko;+

Ó rú jáde bí ìtànná orí pápá.+

16 Àmọ́ nígbà tí atẹ́gùn fẹ́, kò sí mọ́,

Àfi bíi pé kò sí níbẹ̀ rí.*

17 Àmọ́ ìfẹ́ Jèhófà tí kì í yẹ̀ wà títí ayé*

Sí àwọn tó bẹ̀rù rẹ̀+

Àti òdodo rẹ̀ sí àwọn ọmọ ọmọ wọn,+

18 Sí àwọn tó ń pa májẹ̀mú rẹ̀ mọ́+

Àti àwọn tó ń rí i dájú pé àwọn pa àṣẹ rẹ̀ mọ́.

19 Jèhófà ti fìdí ìtẹ́ rẹ̀ múlẹ̀ gbọn-in ní ọ̀run;+

Ìjọba rẹ̀ sì ń ṣàkóso lórí ohun gbogbo.+

20 Ẹ yin Jèhófà, gbogbo ẹ̀yin áńgẹ́lì rẹ̀,+ tí ẹ jẹ́ alágbára ńlá,

Tí ẹ̀ ń ṣe ohun tó sọ,+ tí ẹ sì ń fetí sí ohùn rẹ̀.*

21 Ẹ yin Jèhófà, gbogbo ẹ̀yin ọmọ ogun rẹ̀,+

Ẹ̀yin òjíṣẹ́ rẹ̀ tó ń ṣe ìfẹ́ rẹ̀.+

22 Ẹ yin Jèhófà, gbogbo ẹ̀yin iṣẹ́ rẹ̀,

Ní gbogbo ibi tó ń jọba lé.*

Kí gbogbo ara* mi yin Jèhófà.

104 Jẹ́ kí n* yin Jèhófà.+

Ìwọ Jèhófà Ọlọ́run mi, o tóbi gan-an.+

O fi ògo* àti ọlá ńlá wọ ara rẹ láṣọ.+

 2 O fi ìmọ́lẹ̀+ bora bí aṣọ;

O na ọ̀run bí aṣọ àgọ́.+

 3 Ó tẹ́ igi àjà àwọn yàrá òkè rẹ̀ sínú omi lókè,*+

Ó fi àwọsánmà ṣe kẹ̀kẹ́ ẹṣin rẹ̀,+

Ó ń lọ lórí ìyẹ́ apá ẹ̀fúùfù.+

 4 Ó dá àwọn áńgẹ́lì rẹ̀ ní ẹ̀mí,

Ó dá àwọn òjíṣẹ́ rẹ̀ ní iná tó ń jó nǹkan run.+

 5 Ó ti gbé ayé kalẹ̀ sórí ìpìlẹ̀ rẹ̀;+

A kì yóò ṣí i nípò* títí láé àti láéláé.+

 6 O fi ibú omi bò ó bí aṣọ.+

Omi náà bo àwọn òkè.

 7 Bí wọ́n ṣe gbọ́ ìbáwí rẹ, wọ́n fẹsẹ̀ fẹ;+

Bí wọ́n ṣe gbọ́ ìró ààrá rẹ, ìbẹ̀rù mú kí wọ́n sá lọ

 8 —Àwọn òkè lọ sókè,+ àwọn àfonífojì sì lọ sílẹ̀—

Sí ibi tí o ṣe fún wọn.

 9 O pa ààlà tí wọn ò gbọ́dọ̀ kọjá,+

Kí wọ́n má bàa bo ayé mọ́.

10 Ó ń mú kí omi sun jáde ní àwọn àfonífojì;

Wọ́n ń ṣàn gba àárín àwọn òkè.

11 Wọ́n ń pèsè omi fún gbogbo ẹran inú igbó;

Àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ igbó ń fi wọ́n pa òùngbẹ.

12 Orí àwọn igi tó wà létí wọn ni àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run ń wọ̀ sí;

Wọ́n ń kọrin láàárín àwọn ẹ̀ka tó léwé dáadáa.

13 Ó ń bomi rin àwọn òkè láti àwọn yàrá òkè rẹ̀.+

Iṣẹ́ ọwọ́* rẹ ń tẹ́ ilẹ̀ ayé lọ́rùn.+

14 Ó ń mú kí koríko hù fún àwọn ẹran orí pápá láti jẹ

Àti ewéko fún ìlò aráyé,+

Kí oúnjẹ lè jáde látinú ilẹ̀

15 Àti wáìnì tó ń mú ọkàn èèyàn yọ̀,+

Òróró tó ń mú kí ojú dán

Àti oúnjẹ tó ń gbé ẹ̀mí ẹni kíkú ró.+

16 Àwọn igi Jèhófà rí omi mu,

Àwọn igi kédárì Lẹ́bánónì tó gbìn,

17 Ibẹ̀ ni àwọn ẹyẹ ń kọ́ ìtẹ́ sí.

Ilé ẹyẹ àkọ̀+ wà lórí àwọn igi júnípà.

18 Àwọn òkè gíga wà fún àwọn ewúrẹ́ orí òkè;+

Àwọn àpáta gàǹgà jẹ́ ibi ààbò fún àwọn gara orí àpáta.+

19 Ó dá òṣùpá láti máa sàmì àkókò;

Oòrùn mọ ìgbà tó yẹ kó wọ̀.+

20 O mú kí òkùnkùn ṣú, alẹ́ sì lẹ́,+

Gbogbo ẹranko inú igbó sì ń jẹ̀ kiri.

21 Àwọn ọmọ kìnnìún* ń ké ramúramù nítorí ẹran tí wọ́n fẹ́ pa jẹ,+

Wọ́n sì ń wá oúnjẹ wọn lọ́dọ̀ Ọlọ́run.+

22 Nígbà tí oòrùn bá yọ,

Wọ́n á pa dà, wọ́n á sì lọ dùbúlẹ̀ sínú ihò wọn.

23 Èèyàn á lọ sẹ́nu iṣẹ́ rẹ̀,

Á sì ṣiṣẹ́ títí di àṣálẹ́.

24 Àwọn iṣẹ́ rẹ mà pọ̀ o, Jèhófà!+

Gbogbo wọn lo fi ọgbọ́n ṣe.+

Ayé kún fún àwọn ohun tí o ṣe.

25 Ibẹ̀ ni òkun wà, ó tóbi, ó sì fẹ̀,

Àìmọye ohun alààyè ló wà nínú rẹ̀, èyí tó kéré àti èyí tó tóbi.+

26 Ibẹ̀ ni àwọn ọkọ̀ òkun ti ń rìn

Àti Léfíátánì,*+ tí o dá kí ó lè máa ṣeré nínú rẹ̀.

27 Gbogbo wọn ń dúró dè ọ́

Kí o lè fún wọn ní oúnjẹ lásìkò.+

28 Ohun tí o fún wọn ni wọ́n ń kó jọ.+

Tí o bá ṣí ọwọ́ rẹ, wọ́n á ní ọ̀pọ̀ ohun rere ní ànító.+

29 Tí o bá gbé ojú rẹ pa mọ́, ìdààmú á bá wọn.

Tí o bá mú ẹ̀mí wọn kúrò, wọ́n á kú, wọ́n á sì pa dà sí erùpẹ̀.+

30 Tí o bá rán ẹ̀mí rẹ jáde, a ó dá wọn,+

Ìwọ á sì sọ ojú ilẹ̀ di ọ̀tun.

31 Ògo Jèhófà yóò wà títí láé.

Jèhófà yóò máa yọ̀ lórí àwọn iṣẹ́ rẹ̀.+

32 Ó wo ayé, ayé sì mì tìtì;

Ó fọwọ́ kan àwọn òkè, wọ́n sì rú èéfín.+

33 Màá kọrin sí Jèhófà+ jálẹ̀ ayé mi;

Màá kọ orin ìyìn* sí Ọlọ́run mi ní gbogbo ìgbà tí mo bá fi wà láàyè.+

34 Kí èrò mi dùn mọ́ ọn.*

Èmi yóò máa yọ̀ nínú Jèhófà.

35 Àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ yóò pa rẹ́ kúrò láyé,

Àwọn ẹni burúkú kò sì ní sí mọ́.+

Jẹ́ kí n* yin Jèhófà. Ẹ yin Jáà!*

105 Ẹ fi ọpẹ́ fún Jèhófà,+ ẹ ké pe orúkọ rẹ̀,

Ẹ jẹ́ kí àwọn èèyàn mọ àwọn ohun tí ó ṣe!+

 2 Ẹ kọrin sí i, ẹ fi orin yìn ín,*

Ẹ máa ronú lórí* gbogbo àwọn iṣẹ́ àgbàyanu rẹ̀.+

 3 Ẹ máa fi orúkọ mímọ́ rẹ̀ yangàn.+

Kí ọkàn àwọn tó ń wá Jèhófà máa yọ̀.+

 4 Ẹ máa wá Jèhófà+ àti agbára rẹ̀.

Ẹ máa wá ojú rẹ̀* nígbà gbogbo.

 5 Ẹ máa rántí àwọn iṣẹ́ àgbàyanu tó ti ṣe,

Àwọn iṣẹ́ ìyanu rẹ̀ àti àwọn ìdájọ́ tó kéde,+

 6 Ẹ̀yin ọmọ* Ábúráhámù ìránṣẹ́ rẹ̀,+

Ẹ̀yin ọmọ Jékọ́bù, ẹ̀yin àyànfẹ́ rẹ̀.+

 7 Òun ni Jèhófà Ọlọ́run wa.+

Àwọn ìdájọ́ rẹ̀ kárí ayé.+

 8 Ó ń rántí májẹ̀mú rẹ̀ títí láé,+

Ìlérí tó ṣe* títí dé ẹgbẹ̀rún ìran,+

 9 Májẹ̀mú tó bá Ábúráhámù dá+

Àti ìbúra rẹ̀ fún Ísákì,+

10 Èyí tó gbé kalẹ̀ bí ìlànà fún Jékọ́bù

Àti bíi májẹ̀mú tó wà títí láé fún Ísírẹ́lì,

11 Ó ní, “Màá fún ọ ní ilẹ̀ Kénáánì+

Bí ogún tí a pín fún yín.”+

12 Èyí jẹ́ nígbà tí wọ́n kéré níye,+

Bẹ́ẹ̀ ni, tí wọ́n kéré níye gan-an, tí wọ́n sì jẹ́ àjèjì ní ilẹ̀ náà.+

13 Wọ́n ń rìn kiri láti orílẹ̀-èdè dé orílẹ̀-èdè,

Láti ọ̀dọ̀ ìjọba kan dé ọ̀dọ̀ àwọn èèyàn míì.+

14 Kò gbà kí ẹnikẹ́ni ni wọ́n lára,+

Ṣùgbọ́n nítorí wọn, ó bá àwọn ọba wí,+

15 Ó ní, “Ẹ má fọwọ́ kan àwọn ẹni àmì òróró mi,

Ẹ má sì ṣe ohun búburú sí àwọn wòlíì mi.”+

16 Ó pe ìyàn wá sórí ilẹ̀ náà;+

Ó dí ibi tí búrẹ́dì ń gbà wọlé sọ́dọ̀ wọn.*

17 Ó rán ọkùnrin kan lọ ṣáájú wọn,

Jósẹ́fù, ẹni tí wọ́n tà lẹ́rú.+

18 Wọ́n fi ṣẹkẹ́ṣẹkẹ̀ de ẹsẹ̀ rẹ̀,*+

Wọ́n fi irin de ọrùn rẹ̀;*

19 Títí ọ̀rọ̀ rẹ̀ fi ṣẹ,+

Ọ̀rọ̀ Jèhófà ló yọ́ ọ mọ́.

20 Ọba ní kí wọ́n lọ tú u sílẹ̀,+

Alákòóso àwọn èèyàn náà dá a sílẹ̀.

21 Ó fi í ṣe ọ̀gá lórí agbo ilé rẹ̀

Àti alákòóso lórí gbogbo ohun ìní rẹ̀,+

 22 Kó lè lo àṣẹ lórí* àwọn ìjòyè rẹ̀ bó ṣe fẹ́,*

Kó sì kọ́ àwọn àgbààgbà rẹ̀ ní ọgbọ́n.+

23 Lẹ́yìn náà, Ísírẹ́lì wá sí Íjíbítì,+

Jékọ́bù sì di àjèjì ní ilẹ̀ Hámù.

24 Ọlọ́run mú kí àwọn èèyàn rẹ̀ pọ̀ rẹpẹtẹ;+

Ó mú kí wọ́n lágbára ju àwọn ọ̀tá wọn lọ,+

 25 Àwọn tó jẹ́ kí ọkàn wọn yí pa dà kí wọ́n lè kórìíra àwọn èèyàn rẹ̀,

Kí wọ́n sì dìtẹ̀ mọ́ àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀.+

26 Ó rán Mósè ìránṣẹ́ rẹ̀+

Àti Áárónì,+ ẹni tí ó yàn.

27 Wọ́n ṣe àwọn iṣẹ́ àmì rẹ̀ láàárín wọn,

Àwọn iṣẹ́ ìyanu rẹ̀ ní ilẹ̀ Hámù.+

28 Ó rán òkùnkùn, ilẹ̀ náà sì ṣókùnkùn;+

Wọn kò ṣọ̀tẹ̀ sí ọ̀rọ̀ rẹ̀.

29 Ó sọ omi wọn di ẹ̀jẹ̀,

Ó sì pa ẹja wọn.+

30 Àwọn àkèré ń gbá yìn-ìn ní ilẹ̀ wọn,+

Kódà nínú àwọn yàrá ọba.

31 Ó pàṣẹ pé kí àwọn eṣinṣin mùjẹ̀mùjẹ̀ ya wọlé,

Kí kòkòrò abìyẹ́ tó ń mùjẹ̀ sì bo gbogbo ilẹ̀ wọn.+

32 Ó sọ òjò wọn di yìnyín,

Ó sì rán mànàmáná* sí ilẹ̀ wọn.+

33 Ó kọ lu àjàrà wọn àti igi ọ̀pọ̀tọ́ wọn,

Ó sì ṣẹ́ àwọn igi tó wà ní ilẹ̀ wọn sí wẹ́wẹ́.

34 Ó ní kí àwọn eéṣú ya wọlé,

Àwọn ọmọ eéṣú tí kò níye.+

35 Wọ́n jẹ gbogbo ewéko ilẹ̀ náà,

Wọ́n sì jẹ irè oko wọn.

36 Lẹ́yìn náà, ó pa gbogbo àkọ́bí tó wà ní ilẹ̀ wọn,+

Ìbẹ̀rẹ̀ agbára ìbímọ wọn.

37 Ó mú àwọn èèyàn rẹ̀ jáde tàwọn ti fàdákà àti wúrà;+

Ìkankan lára àwọn ẹ̀yà rẹ̀ kò sì kọsẹ̀.

38 Íjíbítì yọ̀ nígbà tí wọ́n kúrò,

Nítorí ìbẹ̀rù Ísírẹ́lì* ti bò wọ́n.+

39 Ó na àwọsánmà* bo àwọn èèyàn rẹ̀,+

Ó sì pèsè iná láti fún wọn ní ìmọ́lẹ̀ ní òru.+

40 Wọ́n béèrè ẹran, ó sì fún wọn ní àparò;+

Ó ń fi oúnjẹ láti ọ̀run tẹ́ wọn lọ́rùn.+

41 Ó ṣí àpáta, omi sì ṣàn jáde;+

Ó ṣàn gba aṣálẹ̀ kọjá bí odò.+

42 Nítorí ó rántí ìlérí mímọ́ tó ṣe fún Ábúráhámù ìránṣẹ́ rẹ̀.+

43 Torí náà, ó mú àwọn èèyàn rẹ̀ jáde tayọ̀tayọ̀,+

Ó mú àwọn àyànfẹ́ rẹ̀ jáde pẹ̀lú igbe ìdùnnú.

44 Ó fún wọn ní ilẹ̀ àwọn orílẹ̀-èdè;+

Wọ́n jogún ohun tí àwọn míì ti ṣiṣẹ́ kára láti mú jáde,+

45 Kí wọ́n lè máa pa àwọn àṣẹ rẹ̀ mọ́,+

Kí wọ́n sì máa tẹ̀ lé àwọn òfin rẹ̀.

Ẹ yin Jáà!*

106 Ẹ yin Jáà!*

Ẹ fi ọpẹ́ fún Jèhófà, nítorí ó jẹ́ ẹni rere;+

Ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí láé.+

 2 Ta ló lè kéde gbogbo iṣẹ́ ńlá tí Jèhófà ṣe

Tàbí tó lè kéde gbogbo iṣẹ́ rẹ̀ tó yẹ fún ìyìn?+

 3 Aláyọ̀ ni àwọn tó ń ṣe ohun tó bá ẹ̀tọ́ mu,

Àwọn tó ń ṣe ohun tí ó tọ́ nígbà gbogbo.+

 4 Jèhófà, rántí mi nígbà tí o bá ń ṣojú rere sí* àwọn èèyàn rẹ.+

Fi àwọn iṣẹ́ ìgbàlà rẹ tọ́jú mi,

 5 Kí n lè gbádùn oore tí ò ń ṣe fún àwọn àyànfẹ́ rẹ,+

Kí n lè máa bá orílẹ̀-èdè rẹ yọ̀,

Kí n lè máa ṣògo bí mo ṣe ń yìn ọ́* pẹ̀lú ogún rẹ.

 6 A ti dẹ́ṣẹ̀ bí àwọn baba ńlá wa;+

A ti ṣe ohun tí kò dáa; a ti hùwà burúkú.+

 7 Àwọn baba ńlá wa ní Íjíbítì kò mọyì* àwọn iṣẹ́ àgbàyanu rẹ.

Wọn ò rántí ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ tó pọ̀ gidigidi,

Wọ́n ṣọ̀tẹ̀ ní òkun, létí Òkun Pupa.+

 8 Àmọ́, ó gbà wọ́n sílẹ̀ nítorí orúkọ rẹ̀,+

Kí wọ́n lè mọ bí agbára rẹ̀ ṣe pọ̀ tó.+

 9 Ó bá Òkun Pupa wí, ó sì gbẹ;

Ó mú wọn gba ìsàlẹ̀ rẹ̀ bí ẹni gba aṣálẹ̀* kọjá;+

10 Ó gbà wọ́n lọ́wọ́ elénìní,+

Ó sì gbà wọ́n pa dà lọ́wọ́ ọ̀tá.+

11 Omi bo àwọn elénìní wọn;

Kò sí ìkankan lára wọn tó yè bọ́.*+

12 Nígbà náà, wọ́n ní ìgbàgbọ́ nínú ìlérí rẹ̀;+

Wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í kọrin yìn ín.+

13 Àmọ́ kò pẹ́ tí wọ́n fi gbàgbé ohun tó ṣe;+

Wọn ò dúró de ìmọ̀ràn rẹ̀.

14 Wọ́n jẹ́ kí ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ gbà wọ́n lọ́kàn ní aginjù;+

Wọ́n dán Ọlọ́run wò ní aṣálẹ̀.+

15 Ó fún wọn ní ohun tí wọ́n béèrè,

Àmọ́ lẹ́yìn náà, ó fi àrùn kọ lù wọ́n, wọ́n* sì rù hangogo.+

16 Ní ibùdó, wọ́n jowú Mósè

Àti Áárónì,+ ẹni mímọ́ Jèhófà.+

17 Ni ilẹ̀ bá lanu, ó gbé Dátánì mì,

Ó sì bo àwọn tó kóra jọ sọ́dọ̀ Ábírámù.+

18 Iná sọ láàárín àwùjọ wọn;

Ọwọ́ iná jó àwọn ẹni burúkú run.+

19 Wọ́n ṣe ère ọmọ màlúù kan ní Hórébù,

Wọ́n sì forí balẹ̀ fún ère onírin;*+

20 Wọ́n gbé ògo mi

Fún ère akọ màlúù tó ń jẹ koríko.+

21 Wọ́n gbàgbé Ọlọ́run,+ Olùgbàlà wọn,

Ẹni tó ṣe àwọn ohun ńlá ní Íjíbítì,+

22 Àwọn iṣẹ́ àgbàyanu ní ilẹ̀ Hámù,+

Àwọn ohun tó ń bani lẹ́rù ní Òkun Pupa.+

23 Díẹ̀ ló kù kó sọ pé kí wọ́n pa wọ́n rẹ́,

Àmọ́ Mósè àyànfẹ́ rẹ̀ bá wọn bẹ̀bẹ̀*

Láti yí ìbínú rẹ̀ tó ń pani run pa dà.+

24 Síbẹ̀, wọn ò ka ilẹ̀ dáradára náà sí;+

Wọn ò nígbàgbọ́ nínú ìlérí rẹ̀.+

25 Ṣe ni wọ́n ń ráhùn nínú àgọ́ wọn;+

Wọn ò fetí sí ohùn Jèhófà.+

26 Torí náà, ó gbé ọwọ́ rẹ̀ sókè láti búra nípa wọn

Pé òun máa mú kí wọ́n ṣubú ní aginjù;+

27 Pé òun máa mú kí àtọmọdọ́mọ wọn ṣubú láàárín àwọn orílẹ̀-èdè

Àti pé òun máa tú wọn ká sí àwọn ilẹ̀ náà.+

28 Lẹ́yìn náà, wọ́n dara pọ̀ mọ́ àwọn tó ń sin* Báálì Péórì,+

Wọ́n sì ń jẹ ẹbọ tí wọ́n rú sí òkú.*

29 Wọ́n fi àwọn ohun tí wọ́n ń ṣe mú Un bínú,+

Àjàkálẹ̀ àrùn sì bẹ́ sílẹ̀ láàárín wọn.+

30 Àmọ́ nígbà tí Fíníhásì dìde, tí ó sì dá sí i,

Àjàkálẹ̀ àrùn náà dáwọ́ dúró.+

31 A sì kà á sí òdodo fún un

Láti ìran dé ìran àti títí láé.+

32 Wọ́n múnú bí I níbi omi Mẹ́ríbà,*

Wọ́n sì fi tiwọn kó bá Mósè.+

33 Wọ́n gbé ẹ̀mí rẹ̀ gbóná,

Ó sì fi ẹnu rẹ̀ sọ̀rọ̀ láìronú.+

34 Wọn ò pa àwọn èèyàn náà run,+

Bí Jèhófà ṣe pàṣẹ fún wọn.+

35 Àmọ́ wọ́n ń bá àwọn orílẹ̀-èdè náà ṣe wọlé wọ̀de,+

Wọ́n sì ń hùwà bíi tiwọn.*+

36 Wọ́n ń sin àwọn òrìṣà wọn,+

Àwọn òrìṣà náà sì di ìdẹkùn fún wọn.+

37 Wọ́n ń fi àwọn ọmọkùnrin wọn

Àti àwọn ọmọbìnrin wọn rúbọ sí àwọn ẹ̀mí èṣù.+

38 Wọ́n ń ta ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ sílẹ̀,+

Ẹ̀jẹ̀ àwọn ọmọkùnrin wọn àti ti àwọn ọmọbìnrin wọn

Tí wọ́n fi rúbọ sí àwọn òrìṣà Kénáánì;+

Ilẹ̀ náà sì di ẹlẹ́gbin nítorí ìtàjẹ̀sílẹ̀.

39 Àwọn iṣẹ́ wọn sọ wọ́n di aláìmọ́,

Wọ́n sì ṣe àgbèrè ẹ̀sìn.+

40 Torí náà, ìbínú Jèhófà ru sí àwọn èèyàn rẹ̀,

Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í kórìíra ogún rẹ̀.

41 Léraléra ló fi wọ́n lé àwọn orílẹ̀-èdè lọ́wọ́,+

Kí àwọn tó kórìíra wọn lè ṣàkóso lé wọn lórí.+

42 Àwọn ọ̀tá wọn ni wọ́n lára,

Wọ́n sì jẹ gàba lé wọn lórí.*

43 Ọ̀pọ̀ ìgbà ló gbà wọ́n sílẹ̀,+

Àmọ́ wọ́n á ṣọ̀tẹ̀, wọ́n á sì ṣàìgbọràn,+

A ó sì rẹ̀ wọ́n sílẹ̀ nítorí àṣìṣe wọn.+

44 Àmọ́ á tún rí ìdààmú tó bá wọn,+

Á sì gbọ́ igbe ìrànlọ́wọ́ wọn.+

45 Nítorí wọn, á rántí májẹ̀mú rẹ̀,

Àánú á sì ṣe é* nítorí ìfẹ́ rẹ̀ tó ga tí kì í sì í yẹ̀.*+

46 Á jẹ́ kí àánú wọn máa ṣe

Gbogbo àwọn tó mú wọn lẹ́rú.+

47 Gbà wá, Jèhófà Ọlọ́run wa,+

Kí o sì kó wa jọ látinú àwọn orílẹ̀-èdè+

Ká lè máa fi ọpẹ́ fún orúkọ mímọ́ rẹ,

Ká sì máa yọ̀ bí a ṣe ń yìn ọ́.*+

48 Ìyìn ni fún Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì

Títí láé àti láéláé.*+

Kí gbogbo èèyàn sì sọ pé, “Àmín!”*

Ẹ yin Jáà!*

ÌWÉ KARÙN-ÚN

(Sáàmù 107-150)

107 Ẹ fi ọpẹ́ fún Jèhófà, nítorí ó jẹ́ ẹni rere;+

Ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí láé.+

 2 Kí àwọn tí Jèhófà gbà* pa dà sọ bẹ́ẹ̀,

Àwọn tó gbà pa dà lọ́wọ́* ọ̀tá,+

 3 Àwọn tó kó jọ láti àwọn ilẹ̀,+

Láti ìlà oòrùn àti láti ìwọ̀ oòrùn,*

Láti àríwá àti láti gúúsù.+

 4 Wọ́n rìn kiri ní aginjù, ní aṣálẹ̀;

Wọn ò rí ọ̀nà tí wọ́n lè gbà dé ìlú tí wọ́n lè máa gbé.

 5 Ebi pa wọ́n, òùngbẹ sì gbẹ wọ́n;

Àárẹ̀ mú wọn* torí wọn ò lókun mọ́.

 6 Wọ́n ń ké pe Jèhófà nínú wàhálà tó bá wọn,+

Ó sì gbà wọ́n nínú ìnira wọn.+

 7 Ó mú wọn gba ọ̀nà tí ó tọ́+

Kí wọ́n lè dé ìlú tí wọ́n á lè máa gbé.+

 8 Kí àwọn èèyàn máa dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà+ nítorí ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀

Àti nítorí àwọn iṣẹ́ àgbàyanu rẹ̀ lórí àwọn ọmọ èèyàn.+

 9 Nítorí ó mú kí àwọn tí òùngbẹ ń gbẹ mu àmutẹ́rùn,

Ó sì mú kí àwọn* tí ebi ń pa jẹ ohun rere ní àjẹtẹ́rùn.+

10 Àwọn kan ń gbé inú òkùnkùn biribiri,

Àwọn ẹlẹ́wọ̀n tí ìyà ń jẹ, tí ṣẹkẹ́ṣẹkẹ̀ sì wà lọ́wọ́ wọn.

11 Nítorí wọ́n ta ko ọ̀rọ̀ Ọlọ́run;

Wọn ò ka ìmọ̀ràn Ẹni Gíga Jù Lọ sí.+

12 Torí náà, ó fi ìnira rẹ ọkàn wọn sílẹ̀;+

Wọ́n kọsẹ̀, kò sì sí ẹni tó máa ràn wọ́n lọ́wọ́.

13 Wọ́n ké pe Jèhófà fún ìrànlọ́wọ́ nítorí wàhálà tó bá wọn,

Ó sì gbà wọ́n nínú ìnira wọn.

14 Ó mú wọn jáde nínú òkùnkùn biribiri,

Ó sì fa ìdè wọn já.+

15 Kí àwọn èèyàn máa dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà nítorí ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀+

Àti nítorí àwọn iṣẹ́ àgbàyanu rẹ̀ lórí àwọn ọmọ èèyàn.

16 Nítorí ó ti fọ́ àwọn ilẹ̀kùn bàbà,

Ó sì ti gé àwọn ọ̀pá ìdábùú onírin.+

17 Wọ́n ya òmùgọ̀, wọ́n sì jìyà+

Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wọn àti àṣìṣe wọn.+

18 Oúnjẹ kankan ò lọ lẹ́nu wọn;*

Wọ́n sún mọ́ àwọn ẹnubodè ikú.

19 Wọ́n á ké pe Jèhófà fún ìrànlọ́wọ́ nítorí wàhálà tó bá wọn;

Á sì gbà wọ́n nínú ìnira wọn.

20 Á fi ọ̀rọ̀ rẹ̀ ránṣẹ́ sí wọn, á mú wọn lára dá,+

Á sì yọ wọ́n nínú kòtò tí wọ́n há sí.

21 Kí àwọn èèyàn máa dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà nítorí ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀

Àti nítorí àwọn iṣẹ́ àgbàyanu rẹ̀ lórí àwọn ọmọ èèyàn.

22 Kí wọ́n rú ẹbọ ọpẹ́,+

Kí wọ́n sì máa fi igbe ayọ̀ kéde àwọn iṣẹ́ rẹ̀.

23 Àwọn tó ń fi ọkọ̀ rìnrìn àjò lórí òkun,

Tí wọ́n ń ṣòwò lórí agbami òkun,+

 24 Wọ́n ti rí àwọn iṣẹ́ Jèhófà

Àti àwọn iṣẹ́ àgbàyanu rẹ̀ nínú ibú;+

 25 Bó ṣe fi ọ̀rọ̀ rẹ̀ mú kí ìjì máa jà,+

Tó sì ń ru ìgbì òkun sókè.

26 Wọ́n gòkè lọ sí ojú ọ̀run;

Wọ́n já wálẹ̀ ṣòòròṣò sínú ibú.

Ọkàn wọn domi nítorí àjálù tó rọ̀ dẹ̀dẹ̀.

27 Wọ́n ń rìn tàgétàgé, wọ́n sì ń ta gọ̀ọ́gọ̀ọ́ bí ọ̀mùtí,

Gbogbo ọgbọ́n tí wọ́n ní já sí pàbó.+

28 Ni wọ́n bá ké pe Jèhófà nínú wàhálà tó bá wọn,+

Ó sì gbà wọ́n nínú ìnira wọn.

29 Ó mú kí ìjì náà rọlẹ̀,

Ìgbì òkun sì pa rọ́rọ́.+

30 Inú wọn dùn nígbà tí gbogbo rẹ̀ pa rọ́rọ́,

Ó sì ṣamọ̀nà wọn dé èbúté tí wọ́n fẹ́.

31 Kí àwọn èèyàn máa dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà nítorí ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀

Àti nítorí àwọn iṣẹ́ àgbàyanu rẹ̀ lórí àwọn ọmọ èèyàn.+

32 Kí wọ́n máa gbé e ga nínú ìjọ àwọn èèyàn,+

Kí wọ́n sì máa yìn ín nínú ìgbìmọ̀* àwọn àgbààgbà.

33 Ó ń sọ àwọn odò di aṣálẹ̀,

Ó sì ń sọ ìṣàn omi di ilẹ̀ tó gbẹ táútáú,+

 34 Ó ń sọ ilẹ̀ eléso di aṣálẹ̀,+

Nítorí ìwà burúkú àwọn tó ń gbé orí rẹ̀.

35 Ó ń sọ aṣálẹ̀ di adágún omi tí esùsú* kún inú rẹ̀,

Ó sì ń sọ ilẹ̀ gbígbẹ di ìṣàn omi.+

36 Ó ń mú kí àwọn tí ebi ń pa máa gbé ibẹ̀,+

Kí wọ́n lè tẹ ìlú dó láti máa gbé.+

37 Wọ́n dáko, wọ́n sì gbin ọgbà àjàrà+

Tí irè oko rẹ̀ pọ̀ dáadáa.+

38 Ó bù kún wọn, wọ́n sì pọ̀ gidigidi;

Kò jẹ́ kí ẹran ọ̀sìn wọn pẹ̀dín.+

39 Àmọ́ wọ́n tún dín kù, ẹ̀tẹ́ sì bá wọn

Nítorí ìnilára, àjálù àti ẹ̀dùn ọkàn.

40 Ó rọ̀jò àbùkù sórí àwọn èèyàn pàtàkì,

Ó sì mú kí wọ́n rìn kiri ní ilẹ̀ tó ti di ahoro, tí kò sì lójú ọ̀nà.+

41 Àmọ́ ó dáàbò bo àwọn aláìní* lọ́wọ́ ìnilára,+

Ó sì mú kí ìdílé wọn pọ̀ bí agbo ẹran.

42 Àwọn adúróṣinṣin rí èyí, wọ́n sì yọ̀;+

Àmọ́ gbogbo àwọn aláìṣòdodo pa ẹnu wọn mọ́.+

43 Ẹni tó bá gbọ́n yóò kíyè sí àwọn nǹkan yìí,+

Yóò sì fara balẹ̀ kíyè sí àwọn ohun tí Jèhófà ṣe nítorí ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀.+

Orin. Orin Dáfídì.

108 Ọkàn mi dúró ṣinṣin, Ọlọ́run.

Màá fi gbogbo ara* kọrin, màá sì lo ohun ìkọrin.+

 2 Jí, ìwọ ohun ìkọrin olókùn tín-ín-rín; àti ìwọ náà, háàpù.+

Màá jí ní kùtùkùtù.

 3 Jèhófà, màá yìn ọ́ láàárín àwọn èèyàn,

Màá sì fi orin yìn ọ́* láàárín àwọn orílẹ̀-èdè.

 4 Nítorí ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ ga gan-an, ó dé ọ̀run,+

Òtítọ́ rẹ sì ga dé sánmà.

 5 Gbé ara rẹ ga ju ọ̀run lọ, ìwọ Ọlọ́run;

Kí ògo rẹ wà lórí gbogbo ayé.+

 6 Kí a lè gba àwọn olùfẹ́ rẹ sílẹ̀,

Fi ọwọ́ ọ̀tún rẹ gbà wá sílẹ̀, kí o sì dá mi lóhùn.+

 7 Ọlọ́run ti sọ̀rọ̀ nínú ìjẹ́mímọ́* rẹ̀ pé:

“Màá yọ ayọ̀ ìṣẹ́gun, màá fi Ṣékémù+ ṣe ogún fún àwọn èèyàn mi,

Màá sì díwọ̀n Àfonífojì* Súkótù+ fún ẹni tí mo bá fẹ́.

 8 Gílíádì+ jẹ́ tèmi, bí Mánásè ṣe jẹ́ tèmi,

Éfúrémù sì ni akoto* orí mi;+

Júdà ni ọ̀pá àṣẹ mi.+

 9 Móábù ni bàsíà tí mo fi ń wẹ ẹsẹ̀.+

Orí Édómù ni màá ju bàtà mi sí.+

Màá kígbe ìṣẹ́gun lórí Filísíà.”+

10 Ta ló máa mú mi wá sí ìlú olódi?

Ta ló máa mú mi lọ sí Édómù?+

11 Ìwọ Ọlọ́run tí o ti kọ̀ wá sílẹ̀ náà ni,

Ìwọ Ọlọ́run wa, tí o kò bá àwọn ọmọ ogun wa jáde mọ́.+

12 Ràn wá lọ́wọ́ nínú wàhálà wa,+

Nítorí asán ni ìgbàlà látọwọ́ èèyàn.+

13 Ọlọ́run ló máa fún wa lágbára,+

Yóò sì tẹ àwọn ọ̀tá wa rẹ́.+

Sí olùdarí. Ti Dáfídì. Orin.

109 Ìwọ Ọlọ́run tí mò ń yìn,+ má ṣe dákẹ́.

 2 Nítorí àwọn ẹni burúkú àti àwọn ẹlẹ́tàn ń la ẹnu wọn sí mi.

Wọ́n ń fi ahọ́n èké sọ̀rọ̀ nípa mi;+

 3 Wọ́n yí mi ká, wọ́n sì ń sọ̀rọ̀ ìkórìíra sí mi,

Wọ́n ń bá mi jà láìnídìí.+

 4 Mo nífẹ̀ẹ́ wọn, àmọ́ ńṣe ni wọ́n ń ta kò mí;+

Síbẹ̀ mi ò dákẹ́ àdúrà.

 5 Wọ́n ń fi ibi san ire fún mi,+

Wọ́n sì ń fi ìkórìíra san ìfẹ́ tí mo ní sí wọn.+

 6 Yan ẹni burúkú lé e lórí;

Kí alátakò* dúró sí ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀.

 7 Nígbà tí wọ́n bá ṣèdájọ́ rẹ̀, kí ó jẹ̀bi;*

Kí á ka àdúrà rẹ̀ pàápàá sí ẹ̀ṣẹ̀.+

 8 Kí ẹ̀mí rẹ̀ má ṣe gùn;+

Kí ẹlòmíì gba iṣẹ́ àbójútó rẹ̀.+

 9 Kí àwọn ọmọ* rẹ̀ di aláìníbaba,

Kí ìyàwó rẹ̀ sì di opó.

10 Kí àwọn ọmọ* rẹ̀ máa tọrọ nǹkan kiri,

Kí wọ́n sì máa jáde látinú ilé wọn tó ti di ahoro lọ wá oúnjẹ.

11 Kí ẹni tó jẹ ní gbèsè gbẹ́sẹ̀ lé* gbogbo ohun tó ní,

Kí àwọn àjèjì sì kó ohun ìní rẹ̀.

12 Kí ẹnikẹ́ni má ṣe nawọ́ oore* sí i,

Kí ẹnikẹ́ni má sì ṣojú rere sí àwọn ọmọ rẹ̀ tí kò ní bàbá.

13 Kí àtọmọdọ́mọ* rẹ̀ pa rẹ́;+

Kí orúkọ wọn pa rẹ́ kí ìran tó ń bọ̀ tó dé.

14 Kí Jèhófà rántí àṣìṣe àwọn baba ńlá rẹ̀,+

Kí ẹ̀ṣẹ̀ ìyá rẹ̀ má sì pa rẹ́.

15 Kí Jèhófà máa rántí gbogbo ohun tí wọ́n ṣe;

Kí ó sì pa ìrántí wọn rẹ́ kúrò ní ayé.+

16 Nítorí kò rántí ṣe oore,*+

Àmọ́, ó ń lé ẹni tí ìyà ń jẹ+ àti aláìní pẹ̀lú ẹni tó ní ọgbẹ́ ọkàn

Láti pa wọ́n.+

17 Ó fẹ́ràn kó máa gégùn-ún, ohun tó sì dà lé e lórí nìyẹn;

Kì í fẹ́ súre, torí náà, kò rí ìbùkún kankan gbà.

18 Ó gbé ègún wọ̀ bí aṣọ.

Ó dà sínú ara rẹ̀ bí omi,

Ó sì wọnú egungun rẹ̀ bí òróró.

19 Kí ègún wé mọ́ ọn bí aṣọ tó ń wọ̀+

Àti bí àmùrè tó ń dè nígbà gbogbo.

20 Ohun tí Jèhófà máa san fún ẹni tó ń ta kò mí nìyí+

Àti fún àwọn tó ń sọ̀rọ̀ burúkú sí mi.*

21 Àmọ́ ìwọ, Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ,

Gbèjà mi nítorí orúkọ rẹ.+

Gbà mí sílẹ̀, nítorí ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ dára.+

22 Mi ò lè ṣe nǹkan kan, mo jẹ́ aláìní,+

Ọkàn mi sì ti gbọgbẹ́.+

23 Mò ń kọjá lọ bí òjìji tó ń pa rẹ́ lọ;

Wọ́n ti gbọ̀n mí dà nù bí eéṣú.

24 Àwọn eékún mi ti yẹ̀ nítorí ààwẹ̀ gbígbà;

Mo ti rù, mo sì ń kú lọ.*

25 Mo ti di ohun tí wọ́n fi ń ṣe yẹ̀yẹ́.+

Tí wọ́n bá rí mi, ṣe ni wọ́n ń mi orí.+

26 Ràn mí lọ́wọ́, Jèhófà Ọlọ́run mi;

Fi ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ gbà mí.

27 Kí wọ́n mọ̀ pé ọwọ́ rẹ ló ṣe èyí;

Pé ìwọ, Jèhófà, ló ṣe é.

28 Kí wọ́n gégùn-ún, àmọ́ ṣe ni kí o súre fún mi.

Tí wọ́n bá dìde sí mi, jẹ́ kí ojú tì wọ́n,

Àmọ́ kí ìránṣẹ́ rẹ máa yọ̀.

29 Kí ẹ̀tẹ́ bo àwọn tó ń ta kò mí;

Kí wọ́n gbé ìtìjú wọ̀ bí aṣọ.*+

30 Ẹnu mi á máa yin Jèhófà gidigidi;

Màá máa yìn ín níwájú ọ̀pọ̀ èèyàn.+

31 Nítorí á dúró ní ọwọ́ ọ̀tún aláìní

Láti gbà á lọ́wọ́ àwọn tó ń dá a* lẹ́bi.

Ti Dáfídì. Orin.

110 Jèhófà sọ fún Olúwa mi pé:

“Jókòó sí ọwọ́ ọ̀tún mi+

Títí màá fi fi àwọn ọ̀tá rẹ ṣe àpótí ìtìsẹ̀ rẹ.”+

 2 Jèhófà yóò na ọ̀pá agbára rẹ jáde láti Síónì, yóò sọ pé:

“Máa ṣẹ́gun lọ láàárín àwọn ọ̀tá rẹ.”+

 3 Àwọn èèyàn rẹ máa yọ̀ǹda ara wọn tinútinú ní ọjọ́ ìjáde ogun rẹ.*

Nínú ọlá ńlá ìjẹ́mímọ́, láti ibi tí ọ̀yẹ̀ ti ń là,*

O ní àwùjọ àwọn ọ̀dọ́ tí wọ́n rí bí ìrì tó ń sẹ̀.

 4 Jèhófà ti búra, kò sì ní pèrò dà,* ó ní:

“Ìwọ jẹ́ àlùfáà títí láé+

Ní ọ̀nà ti Melikisédékì!”+

 5 Jèhófà yóò wà ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ;+

Yóò fọ́ àwọn ọba túútúú ní ọjọ́ ìbínú rẹ̀.+

 6 Yóò mú ìdájọ́ ṣẹ lórí* àwọn orílẹ̀-èdè;+

Yóò fi òkú kún ilẹ̀ náà.+

Yóò fọ́ aṣáájú* ilẹ̀ fífẹ̀* túútúú.

 7 Yóò* mu omi odò tó wà lójú ọ̀nà,

Yóò sì gbé orí rẹ̀ sókè.

111 Ẹ yin Jáà!*+

א [Áléfì]

Màá fi gbogbo ọkàn mi yin Jèhófà+

ב [Bétì]

Nínú àwùjọ àwọn adúróṣinṣin àti nínú ìjọ.

ג [Gímélì]

 2 Àwọn iṣẹ́ Jèhófà tóbi;+

ד [Dálétì]

Gbogbo àwọn tó fẹ́ràn wọn máa ń kẹ́kọ̀ọ́ nípa wọn.+

ה [Híì]

 3 Àwọn iṣẹ́ rẹ̀ ní ògo àti ọlá ńlá,

ו [Wọ́ọ̀]

Òdodo rẹ̀ sì wà títí láé.+

ז [Sáyìn]

 4 Ó ń mú ká rántí àwọn iṣẹ́ àgbàyanu rẹ̀.+

ח [Hétì]

Jèhófà jẹ́ agbatẹnirò* àti aláàánú.+

ט [Tétì]

 5 Ó ń fún àwọn tó bẹ̀rù rẹ̀ ní oúnjẹ.+

י [Yódì]

Ó rántí májẹ̀mú rẹ̀ títí láé.+

כ [Káfì]

 6 Ó ti fi àwọn iṣẹ́ agbára rẹ̀ han àwọn èèyàn rẹ̀

ל [Lámédì]

Bó ṣe fún wọn ní ogún àwọn orílẹ̀-èdè.+

מ [Mémì]

 7 Àwọn iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀ jẹ́ òtítọ́ àti ìdájọ́ òdodo;+

נ [Núnì]

Gbogbo àṣẹ rẹ̀ ṣeé gbẹ́kẹ̀ lé.+

ס [Sámékì]

 8 Wọ́n ṣeé gbára lé ní gbogbo ìgbà, ní báyìí àti títí láé;

ע [Áyìn]

Inú òtítọ́ àti òdodo ni wọ́n ti wá.+

פ [Péè]

 9 Ó ti ra àwọn èèyàn rẹ̀ pa dà,+

צ [Sádì]

Ó pàṣẹ pé kí májẹ̀mú rẹ̀ wà títí láé.

ק [Kófì]

Orúkọ rẹ̀ jẹ́ mímọ́, ó sì yẹ fún ọ̀wọ̀.+

ר [Réṣì]

10 Ìbẹ̀rù Jèhófà ni ìbẹ̀rẹ̀ ọgbọ́n.+

ש [Sínì]

Gbogbo àwọn tó ń pa àwọn àṣẹ rẹ̀* mọ́ ní òye tó jinlẹ̀ gan-an.+

ת [Tọ́ọ̀]

Ìyìn rẹ̀ wà títí láé.

112 Ẹ yin Jáà!*+

א [Áléfì]

Aláyọ̀ ni ẹni tó bẹ̀rù Jèhófà,+

ב [Bétì]

Tó sì fẹ́ràn àwọn àṣẹ rẹ̀ gan-an.+

ג [Gímélì]

 2 Àtọmọdọ́mọ rẹ̀ yóò di alágbára ní ayé,

ד [Dálétì]

Ìran àwọn adúróṣinṣin yóò sì rí ìbùkún.+

ה [Híì]

 3 Ọlá àti ọrọ̀ wà nínú ilé rẹ̀,

ו [Wọ́ọ̀]

Òdodo rẹ̀ sì wà títí láé.

ז [Sáyìn]

 4 Nínú òkùnkùn, ó ń tàn yanran bí ìmọ́lẹ̀ sí àwọn adúróṣinṣin.+

ח [Hétì]

Ó jẹ́ agbatẹnirò* àti aláàánú+ àti olódodo.

ט [Tétì]

 5 Nǹkan máa ń lọ dáadáa fún ẹni tó bá ń yáni ní nǹkan tọkàntọkàn.*+

י [Yódì]

Ìdájọ́ òdodo ló fi ń ṣe nǹkan.

כ [Káfì]

 6 Mìmì kan ò ní mì í láé.+

ל [Lámédì]

A ó máa rántí àwọn olódodo títí láé.+

מ [Mémì]

 7 Kò ní bẹ̀rù ìròyìn burúkú.+

נ [Núnì]

Ọkàn rẹ̀ dúró ṣinṣin, ó gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà.+

ס [Sámékì]

 8 Ọkàn rẹ̀ kò mì;* kò bẹ̀rù;+

ע [Áyìn]

Níkẹyìn, yóò rí ìṣubú àwọn ọ̀tá rẹ̀.+

פ [Péè]

 9 Ó ti pín nǹkan fún àwọn èèyàn káàkiri;* ó ti fún àwọn aláìní.+

צ [Sádì]

Òdodo rẹ̀ wà títí láé.+

ק [Kófì]

A ó gbé agbára* rẹ̀ ga nínú ògo.

ר [Réṣì]

10 Ẹni burúkú á rí i, inú á sì bí i.

ש [Ṣínì]

Á wa eyín pọ̀, á sì pa rẹ́.

ת [Tọ́ọ̀]

Ìfẹ́ ọkàn àwọn ẹni burúkú yóò ṣègbé.+

113 Ẹ yin Jáà!*

Ẹ mú ìyìn wá, ẹ̀yin ìránṣẹ́ Jèhófà,

Ẹ yin orúkọ Jèhófà.

 2 Kí á máa yin orúkọ Jèhófà

Láti ìsinsìnyí lọ àti títí láé.+

 3 Láti yíyọ oòrùn títí dé wíwọ̀ rẹ̀,

Kí á máa yin orúkọ Jèhófà.+

 4 Jèhófà ga ju gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè;+

Ògo rẹ̀ ga ju ọ̀run lọ.+

 5 Ta ló dà bíi Jèhófà Ọlọ́run wa,+

Ẹni tó ń gbé* ibi gíga?

 6 Ó tẹ̀ ba láti wo ọ̀run àti ayé,+

 7 Ó ń gbé aláìní dìde látinú eruku.

Ó ń gbé tálákà dìde látorí eérú*+

 8 Kí ó lè mú un jókòó pẹ̀lú àwọn èèyàn pàtàkì,

Àwọn ẹni pàtàkì nínú àwọn èèyàn rẹ̀.

 9 Ó ń fún àgàn ní ilé

Kí ó lè di abiyamọ aláyọ̀, ìyá àwọn ọmọ.*+

Ẹ yin Jáà!*

114 Nígbà tí Ísírẹ́lì jáde kúrò ní Íjíbítì,+

Tí ilé Jékọ́bù jáde kúrò lọ́dọ̀ àwọn tó ń sọ èdè àjèjì,

 2 Júdà di ibi mímọ́ rẹ̀,

Ísírẹ́lì di ibi tó ń ṣàkóso lé lórí.+

 3 Òkun rí i, ó sì sá lọ;+

Odò Jọ́dánì yíjú pa dà.+

 4 Àwọn òkè ńlá ń ta pọ́n-ún pọ́n-ún kiri bí àgbò,+

Àwọn òkè kéékèèké ń ta bí ọ̀dọ́ àgùntàn.

 5 Kí ló lé ọ léré, ìwọ òkun?+

Kí ló dé tí o fi yíjú pa dà, ìwọ Jọ́dánì?+

 6 Kí ló dé tí ẹ̀yin òkè ńlá fi ń ta pọ́n-ún pọ́n-ún kiri bí àgbò,

Tí ẹ̀yin òkè kéékèèké sì ń ta bí ọ̀dọ́ àgùntàn?

 7 Máa gbọ̀n jìnnìjìnnì nítorí Olúwa, ìwọ ayé,

Nítorí Ọlọ́run Jékọ́bù,+

 8 Ẹni tó ń sọ àpáta di adágún omi tí esùsú* kún inú rẹ̀,

Tó ń sọ akọ àpáta di ìsun omi.+

115 Kì í ṣe àwa, Jèhófà, kì í ṣe àwa,*

Àmọ́ orúkọ rẹ ni ògo yẹ+

Nítorí ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ àti òtítọ́ rẹ.+

 2 Ṣé ó yẹ kí àwọn orílẹ̀-èdè sọ pé:

“Ọlọ́run wọn dà?”+

 3 Ọlọ́run wa wà ní ọ̀run;

Ó ń ṣe ohun tí ó bá fẹ́.

 4 Àwọn òrìṣà wọn jẹ́ fàdákà àti wúrà,

Iṣẹ́ ọwọ́ èèyàn.+

 5 Wọ́n ní ẹnu, àmọ́ wọn ò lè sọ̀rọ̀;+

Wọ́n ní ojú, àmọ́ wọn ò lè ríran;

 6 Wọ́n ní etí, àmọ́ wọn ò lè gbọ́ràn;

Wọ́n ní imú, àmọ́ wọn ò lè gbóòórùn;

 7 Wọ́n ní ọwọ́, àmọ́ wọn ò lè fọwọ́ ba nǹkan;

Wọ́n ní ẹsẹ̀, àmọ́ wọn ò lè rìn;+

Wọn ò lè mú ìró kankan jáde láti ọ̀fun wọn.+

 8 Àwọn tó ń ṣe wọ́n yóò dà bíi wọn gẹ́lẹ́,+

Bẹ́ẹ̀ ló sì ṣe máa rí fún gbogbo àwọn tó gbẹ́kẹ̀ lé wọn.+

 9 Ísírẹ́lì, gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà+

—Òun ni olùrànlọ́wọ́ wọn àti apata wọn.+

10 Ilé Áárónì,+ ẹ gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà

—Òun ni olùrànlọ́wọ́ wọn àti apata wọn.

11 Ẹ̀yin tí ẹ bẹ̀rù Jèhófà, ẹ gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà+

—Òun ni olùrànlọ́wọ́ wọn àti apata wọn.+

12 Jèhófà ń rántí wa, á sì bù kún wa;

Á bù kún ilé Ísírẹ́lì;+

Á bù kún ilé Áárónì.

13 Á bù kún àwọn tó bẹ̀rù Jèhófà,

Àti ẹni kékeré àti ẹni ńlá.

14 Jèhófà máa mú kí ẹ pọ̀ sí i,

Ẹ̀yin àti àwọn ọmọ* yín.+

15 Kí Jèhófà bù kún yín,+

Aṣẹ̀dá ọ̀run àti ayé.+

16 Ní ti ọ̀run, ti Jèhófà ni,+

Àmọ́ ayé ni ó fún àwọn ọmọ èèyàn.+

17 Àwọn òkú kì í yin Jáà;+

Bẹ́ẹ̀ ni ẹnikẹ́ni tó sọ̀ kalẹ̀ lọ sínú ìdákẹ́jẹ́ẹ́ ikú.*+

18 Àmọ́ a ó máa yin Jáà

Láti ìsinsìnyí lọ àti títí láé.

Ẹ yin Jáà!*

116 Mo nífẹ̀ẹ́ Jèhófà

Nítorí ó ń gbọ́* ohùn mi, ẹ̀bẹ̀ mi fún ìrànlọ́wọ́.+

 2 Nítorí ó ń tẹ́tí* sí mi,+

Èmi yóò máa ké pè é ní gbogbo ìgbà tí mo bá wà láàyè.*

 3 Àwọn okùn ikú yí mi ká;

Isà Òkú dì mí mú.*+

Ìdààmú àti ẹ̀dùn ọkàn bò mí mọ́lẹ̀.+

 4 Àmọ́ mo ké pe orúkọ Jèhófà,+ mo ní:

“Jèhófà, gbà mí* sílẹ̀!”

 5 Jèhófà jẹ́ agbatẹnirò* àti olódodo;+

Ọlọ́run wa jẹ́ aláàánú.+

 6 Jèhófà ń ṣọ́ àwọn aláìmọ̀kan.+

Wọ́n rẹ̀ mí sílẹ̀, àmọ́ ó gbà mí.

 7 Kí ọkàn* mi rí ìsinmi lẹ́ẹ̀kan sí i,

Nítorí Jèhófà ti fi inú rere hàn sí mi.

 8 O ti gbà mí* lọ́wọ́ ikú,

O gba ojú mi lọ́wọ́ omijé, o sì gba ẹsẹ̀ mi lọ́wọ́ ìkọ̀sẹ̀.+

 9 Ṣe ni èmi yóò máa rìn níwájú Jèhófà ní ilẹ̀ alààyè.

10 Mo nígbàgbọ́, torí náà mo sọ̀rọ̀;+

Ìyà jẹ mí gan-an.

11 Ní tèmi, jìnnìjìnnì bò mí, mo sọ pé:

“Òpùrọ́ ni gbogbo èèyàn.”+

12 Kí ni màá san pa dà fún Jèhófà

Lórí gbogbo oore tó ṣe fún mi?

13 Màá gbé ife ìgbàlà,*

Màá sì ké pe orúkọ Jèhófà.

14 Màá san àwọn ẹ̀jẹ́ mi fún Jèhófà

Níwájú gbogbo àwọn èèyàn rẹ̀.+

15 Lójú Jèhófà, àdánù ńlá*

Ni ikú àwọn ẹni ìdúróṣinṣin rẹ̀.+

16 Mo bẹ̀ ọ́, Jèhófà,

Nítorí ìránṣẹ́ rẹ ni mí.

Ìránṣẹ́ rẹ ni mí, ọmọ ẹrúbìnrin rẹ.

O ti tú ìdè mi.+

17 Màá rú ẹbọ ọpẹ́ sí ọ;+

Màá ké pe orúkọ Jèhófà.

18 Màá san àwọn ẹ̀jẹ́ mi fún Jèhófà+

Níwájú gbogbo àwọn èèyàn rẹ̀,+

19 Nínú àwọn àgbàlá ilé Jèhófà,+

Láàárín rẹ, ìwọ Jerúsálẹ́mù.

Ẹ yin Jáà!*+

117 Ẹ yin Jèhófà, gbogbo ẹ̀yin orílẹ̀-èdè;+

Ẹ gbé e ga, gbogbo ẹ̀yin èèyàn.*+

 2 Nítorí ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ tó ní sí wa pọ̀ gan-an;+

Òtítọ́+ Jèhófà wà títí láé.+

Ẹ yin Jáà!*+

118 Ẹ fi ọpẹ́ fún Jèhófà, nítorí ó jẹ́ ẹni rere;+

Ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí láé.

 2 Kí Ísírẹ́lì sọ pé:

“Ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí láé.”

 3 Kí àwọn ará ilé Áárónì sọ pé:

“Ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí láé.”

 4 Kí àwọn tó ń bẹ̀rù Jèhófà sọ pé:

“Ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí láé.”

 5 Mo ké pe Jáà* nínú wàhálà mi;

Jáà dá mi lóhùn, ó sì mú mi wá síbi ààbò.*+

 6 Jèhófà wà lẹ́yìn mi; mi ò ní bẹ̀rù.+

Kí ni èèyàn lè fi mí ṣe?+

 7 Jèhófà wà lẹ́yìn mi láti ràn mí lọ́wọ́;*+

Màá rí ìṣubú àwọn tó kórìíra mi.+

 8 Ó sàn láti fi Jèhófà ṣe ibi ààbò

Ju láti gbẹ́kẹ̀ lé èèyàn.+

 9 Ó sàn láti fi Jèhófà ṣe ibi ààbò

Ju láti gbẹ́kẹ̀ lé àwọn olórí.+

10 Gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè yí mi ká,

Àmọ́ ní orúkọ Jèhófà,

Mo lé wọn sẹ́yìn.+

11 Wọ́n yí mi ká, bẹ́ẹ̀ ni, wọ́n yí mi ká pátápátá,

Àmọ́ ní orúkọ Jèhófà,

Mo lé wọn sẹ́yìn.

12 Wọ́n yí mi ká bí oyin,

Àmọ́ wọ́n kú kíákíá bí iná ẹ̀gún.

Ní orúkọ Jèhófà,

Mo lé wọn sẹ́yìn.+

13 Wọ́n* fi agbára tì mí kí n lè ṣubú,

Àmọ́ Jèhófà ràn mí lọ́wọ́.

14 Jáà ni ibi ààbò mi àti agbára mi,

Ó sì ti di ìgbàlà mi.+

15 Ìró ayọ̀ àti ti ìgbàlà*

Wà ní àgọ́ àwọn olódodo.

Ọwọ́ ọ̀tún Jèhófà ń fi agbára rẹ̀ hàn.+

16 Ọwọ́ ọ̀tún Jèhófà ń ṣẹ́gun;

Ọwọ́ ọ̀tún Jèhófà ń fi agbára rẹ̀ hàn.+

17 Mi ò ní kú, ṣe ni màá wà láàyè,

Kí n lè máa kéde àwọn iṣẹ́ Jáà.+

18 Jáà bá mi wí gan-an,+

Àmọ́ kò fi mí lé ikú lọ́wọ́.+

19 Ẹ ṣí àwọn ẹnubodè òdodo fún mi;+

Màá wọ inú wọn, màá sì yin Jáà.

20 Ẹnubodè Jèhófà nìyí.

Olódodo yóò gba ibẹ̀ wọlé.+

21 Màá yìn ọ́, nítorí o dá mi lóhùn,+

O sì di ìgbàlà mi.

22 Òkúta tí àwọn kọ́lékọ́lé kọ̀ sílẹ̀

Ti di olórí òkúta igun ilé.*+

23 Ọ̀dọ̀ Jèhófà ni èyí ti wá;+

Ó jẹ́ ohun ìyanu lójú wa.+

24 Ọjọ́ tí Jèhófà dá nìyí;

Inú wa yóò máa dùn, a ó sì máa yọ̀ nínú rẹ̀.

25 Jèhófà, a bẹ̀ ọ́, jọ̀wọ́ gbà wá!

Jèhófà, jọ̀wọ́ fún wa ní ìṣẹ́gun!

26 Ìbùkún ni fún ẹni tó ń bọ̀ ní orúkọ Jèhófà;+

À ń bù kún yín látinú ilé Jèhófà.

27 Jèhófà ni Ọlọ́run;

Ó ń fún wa ní ìmọ́lẹ̀.+

Ẹ já ewé dání, kí ẹ sì dara pọ̀ mọ́ àwọn tó ń kọ́wọ̀ọ́ rìn lọ síbi àjọyọ̀,+

Títí dé ibi àwọn ìwo pẹpẹ.+

28 Ìwọ ni Ọlọ́run mi, màá yìn ọ́;

Ìwọ Ọlọ́run mi, màá gbé ọ ga.+

29 Ẹ fi ọpẹ́ fún Jèhófà,+ nítorí ó jẹ́ ẹni rere;

Ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí láé.+

א [Áléfì]

119 Aláyọ̀ ni àwọn tí wọ́n jẹ́ aláìlẹ́bi* ní ọ̀nà wọn,

Àwọn tó ń rìn nínú òfin Jèhófà.+

 2 Aláyọ̀ ni àwọn tó ń kíyè sí àwọn ìránnilétí rẹ̀,+

Àwọn tó ń fi gbogbo ọkàn wọn wá a.+

3 Wọn kì í hùwà àìṣòdodo;

Wọ́n ń rìn ní àwọn ọ̀nà rẹ̀.+

4 O ti pàṣẹ pé

Kí a máa pa òfin rẹ mọ́ délẹ̀délẹ̀.+

5 Ká ní mo lè máa jẹ́ adúróṣinṣin nìṣó*+

Kí n lè máa pa àwọn ìlànà rẹ mọ́!

6 Nígbà náà, ojú ò ní tì mí+

Tí mo bá ń ronú nípa gbogbo àṣẹ rẹ.

7 Màá fi ọkàn tó dúró ṣinṣin yìn ọ́

Nígbà tí mo bá kọ́ nípa àwọn ìdájọ́ rẹ tó jẹ́ òdodo.

8 Màá pa àwọn ìlànà rẹ mọ́.

Má fi mí sílẹ̀ pátápátá.

ב [Bétì]

9 Báwo ni ọ̀dọ́kùnrin ṣe lè mú ipa ọ̀nà rẹ̀ mọ́?

Tó bá ń kíyè sára, tó sì ń pa ọ̀rọ̀ rẹ mọ́.+

10 Gbogbo ọkàn mi ni mo fi wá ọ.

Má ṣe jẹ́ kí n yà kúrò nínú àwọn àṣẹ rẹ.+

11 Mo fi ọ̀rọ̀ rẹ ṣe ìṣúra nínú ọkàn mi+

Kí n má bàa dẹ́ṣẹ̀ sí ọ.+

12 Ìyìn ni fún ọ, Jèhófà;

Kọ́ mi ní àwọn ìlànà rẹ.

13 Mo fi ètè mi kéde

Gbogbo àwọn ìdájọ́ tí o ti ṣe.

14 Àwọn ìránnilétí rẹ ń mú inú mi dùn+

Ju gbogbo àwọn ohun míì tó ṣeyebíye.+

15 Màá máa ronú lórí* àwọn àṣẹ rẹ,+

Màá sì máa fojú sí àwọn ọ̀nà rẹ.+

16 Mo fẹ́ràn àwọn òfin rẹ.

Mi ò ní gbàgbé ọ̀rọ̀ rẹ.+

ג [Gímélì]

17 Ṣe dáadáa sí èmi ìránṣẹ́ rẹ,

Kí n lè wà láàyè, kí n sì máa pa ọ̀rọ̀ rẹ mọ́.+

18 La ojú mi kí n lè rí

Àwọn ohun àgbàyanu tó wà nínú òfin rẹ kedere.

19 Àjèjì lásán ni mí lórí ilẹ̀ yìí.+

Má fi àwọn àṣẹ rẹ pa mọ́ fún mi.

20 Ìfẹ́ àwọn ìdájọ́ rẹ

Gbà mí lọ́kàn nígbà gbogbo.

21 O bá àwọn tó ń kọjá àyè wọn wí,

Àwọn ẹni ègún tó ń yà kúrò nínú àwọn àṣẹ rẹ.+

22 Mú ẹ̀gàn àti àbùkù kúrò lára mi,*

Nítorí pé mo ti kíyè sí àwọn ìránnilétí rẹ.

23 Kódà nígbà tí àwọn olórí bá jọ jókòó, tí wọ́n sì ń sọ̀rọ̀ mi láìdáa,

Àwọn ìlànà rẹ ni èmi ìránṣẹ́ rẹ ń ronú lé lórí.*

24 Mo fẹ́ràn àwọn ìránnilétí rẹ;+

Àwọn ló ń gbà mí nímọ̀ràn.+

ד [Dálétì]

25 Mo* dùbúlẹ̀ nínú eruku.+

Mú kí n máa wà láàyè bí o ṣe sọ.+

26 Mo sọ àwọn ọ̀nà mi fún ọ, o sì dá mi lóhùn;

Kọ́ mi ní àwọn ìlànà rẹ.+

27 Jẹ́ kí n mọ ìtumọ̀* àwọn àṣẹ rẹ,

Kí n lè máa ronú lórí* àwọn iṣẹ́ àgbàyanu rẹ.+

28 Ẹ̀dùn ọkàn ò jẹ́ kí n* rí oorun sùn.

Fún mi lókun bí o ṣe sọ.

29 Mú ọ̀nà ẹ̀tàn kúrò lọ́dọ̀ mi,+

Kí o sì fi òfin rẹ ṣojú rere sí mi.

30 Mo ti yan ọ̀nà òdodo.+

Mo gbà pé àwọn ìdájọ́ rẹ tọ̀nà.

31 Mo rọ̀ mọ́ àwọn ìránnilétí rẹ.+

Jèhófà, má ṣe jẹ́ kí n rí ìjákulẹ̀.*+

32 Màá yára rìn ní* ọ̀nà àwọn àṣẹ rẹ,

Torí pé o ti wá àyè fún un nínú ọkàn mi.*

ה [Híì]

33 Jèhófà,+ kọ́ mi kí n lè máa tè lé àwọn ìlànà rẹ,

Màá sì tẹ̀ lé e délẹ̀délẹ̀.+

34 Jẹ́ kí n ní òye,

Kí n lè máa tẹ̀ lé òfin rẹ,

Kí n sì máa fi gbogbo ọkàn mi pa á mọ́.

35 Darí mi* ní ọ̀nà àwọn àṣẹ rẹ,+

Torí ó ń mú inú mi dùn.

36 Mú kí ọkàn mi máa fà sí àwọn ìránnilétí rẹ,

Kó má ṣe fà sí èrè tí kò tọ́.*+

37 Yí ojú mi kúrò kí n má ṣe máa wo ohun tí kò ní láárí;+

Mú kí n máa wà láàyè ní ọ̀nà rẹ.

38 Mú ìlérí tí o ṣe* fún ìránṣẹ́ rẹ ṣẹ,

Ká lè máa bẹ̀rù rẹ.*

39 Mú ìtìjú tí mò ń bẹ̀rù kúrò,

Nítorí àwọn ìdájọ́ rẹ dára.+

40 Wo bí ọkàn mi ṣe ń fà sí àwọn àṣẹ rẹ.

Mú kí n máa wà láàyè nínú òdodo rẹ.

ו [Wọ́ọ̀]

41 Jèhófà, jẹ́ kí n rí ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀,+

Kí n rí ìgbàlà rẹ bí o ti ṣèlérí;*+

42 Nígbà náà, màá fún ẹni tó ń pẹ̀gàn mi lésì,

Nítorí mo gbẹ́kẹ̀ lé ọ̀rọ̀ rẹ.

43 Má ṣe mú ọ̀rọ̀ òtítọ́ kúrò ní ẹnu mi,

Nítorí mo gbẹ́kẹ̀ lé* ìdájọ́ rẹ.

44 Èmi yóò máa pa òfin rẹ mọ́ nígbà gbogbo,

Títí láé àti láéláé.+

45 Èmi yóò máa rìn káàkiri ní ibi ààbò,*+

Nítorí mò ń wá àwọn àṣẹ rẹ.

46 Èmi yóò máa sọ̀rọ̀ nípa àwọn ìránnilétí rẹ níwájú àwọn ọba,

Mi ò sì ní tijú.+

47 Mo fẹ́ràn àwọn àṣẹ rẹ,

Àní, mo nífẹ̀ẹ́ wọn.+

48 Màá tẹ́ ọwọ́ mi sókè sí ọ nítorí àwọn àṣẹ rẹ, torí mo nífẹ̀ẹ́ wọn,+

Màá sì máa ronú lórí* àwọn ìlànà rẹ.+

ז [Sáyìn]

49 Rántí ọ̀rọ̀ tí o sọ* fún ìránṣẹ́ rẹ,

Èyí tí o fi mú kí n nírètí.*

50 Ohun tó ń tù mí nínú nìyí nínú ìpọ́njú mi,+

Ọ̀rọ̀ rẹ ló ń mú kí n wà láàyè.

51 Àwọn tó ń kọjá àyè wọn kàn mí lábùkù,

Àmọ́ mi ò yà kúrò nínú òfin rẹ.+

52 Jèhófà, mo rántí àwọn ìdájọ́ rẹ ti ìgbà àtijọ́,+

Wọ́n sì ń tù mí nínú.+

53 Mo gbaná jẹ gidigidi nítorí àwọn ẹni burúkú

Tó ń pa òfin rẹ tì.+

54 Orin ni àwọn ìlànà rẹ jẹ́ fún mi

Níbikíbi tí mo bá ń gbé.*

55 Jèhófà, mò ń rántí orúkọ rẹ ní òru,+

Kí n lè máa pa òfin rẹ mọ́.

56 Ó ti jẹ́ ìṣe mi,

Nítorí pé mo ti pa àwọn àṣẹ rẹ mọ́.

ח [Hétì]

57 Jèhófà, ìwọ ni ìpín mi;+

Mo ti ṣèlérí pé màá pa àwọn ọ̀rọ̀ rẹ mọ́.+

58 Mo fi gbogbo ọkàn mi bẹ̀ ọ́;*+

Ṣojú rere sí mi+ bí o ti ṣèlérí.*

59 Mo ti yẹ àwọn ọ̀nà mi wò,

Kí n lè yí ẹsẹ̀ mi pa dà sí àwọn ìránnilétí rẹ.+

60 Mo yára, mi ò sì jáfara

Láti pa àwọn àṣẹ rẹ mọ́.+

61 Okùn àwọn ẹni burúkú yí mi ká,

Àmọ́ mi ò gbàgbé òfin rẹ.+

62 Mo jí ní ọ̀gànjọ́ òru kí n lè dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ+

Nítorí àwọn ìdájọ́ rẹ tó jẹ́ òdodo.

63 Ọ̀rẹ́ mi ni gbogbo àwọn tó bẹ̀rù rẹ

Àti àwọn tó ń pa àwọn àṣẹ rẹ mọ́.+

64 Jèhófà, ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ kún inú ayé;+

Kọ́ mi ní àwọn ìlànà rẹ.

ט [Tétì]

65 Jèhófà, gẹ́gẹ́ bí o ṣe sọ,

O ti hùwà sí ìránṣẹ́ rẹ lọ́nà tó dáa.

66 Kọ́ mi kí n lè ní làákàyè àti ìmọ̀,+

Nítorí àwọn àṣẹ rẹ ni mo gbẹ́kẹ̀ lé.

67 Kí a tó fìyà jẹ mí, mo máa ń ṣe ségesège,*

Àmọ́ ní báyìí, ohun tí o sọ ni mò ń ṣe.+

68 Ẹni rere ni ọ́,+ àwọn iṣẹ́ rẹ sì dára.

Kọ́ mi ní àwọn ìlànà rẹ.+

69 Àwọn tó ń kọjá àyè wọn ti fi irọ́ yí mi lára,

Àmọ́ mò ń fi gbogbo ọkàn mi pa àwọn àṣẹ rẹ mọ́.

70 Ọkàn wọn ti yigbì,*+

Àmọ́ mo fẹ́ràn òfin rẹ.+

71 Ó dára bí a ṣe fìyà jẹ mí,+

Kí n lè kọ́ àwọn ìlànà rẹ.

72 Òfin tí o kéde dára fún mi,+

Ó dára ju ẹgbẹẹgbẹ̀rún wúrà àti fàdákà lọ.+

י [Yódì]

73 Ọwọ́ rẹ ni ó dá mi, tí ó sì mọ mí.

Fún mi ní òye,+

Kí n lè kọ́ àwọn àṣẹ rẹ.

74 Àwọn tó bẹ̀rù rẹ rí mi, wọ́n sì ń yọ̀,

Nítorí ọ̀rọ̀ rẹ ni ìrètí mi.*+

75 Jèhófà, mo mọ̀ pé àwọn ìdájọ́ rẹ jẹ́ òdodo+

Àti pé nínú òtítọ́ rẹ ni o fìyà jẹ mí.+

76 Jọ̀wọ́, jẹ́ kí ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀+ tù mí nínú,

Gẹ́gẹ́ bí ìlérí tí o ṣe* fún ìránṣẹ́ rẹ.

77 Ṣàánú mi, kí n lè máa wà láàyè,+

Nítorí mo fẹ́ràn òfin rẹ.+

78 Kí ojú ti àwọn tó ń kọjá àyè wọn,

Nítorí wọ́n ń ṣe ohun tí kò dáa sí mi láìnídìí.*

Àmọ́ èmi yóò máa ronú lórí* àwọn àṣẹ rẹ.+

79 Kí àwọn tó bẹ̀rù rẹ pa dà sọ́dọ̀ mi,

Àwọn tó mọ ìránnilétí rẹ.

80 Kí ọkàn mi jẹ́ aláìlẹ́bi bí mo ṣe ń tẹ̀ lé àwọn ìlànà rẹ,+

Kí ojú má bàa tì mí.+

כ [Káfì]

81 Ọkàn mi ń fà sí* ìgbàlà rẹ,+

Nítorí ọ̀rọ̀ rẹ ni ìrètí mi.*

82 Ojú mi fẹ́ máa rí ọ̀rọ̀ rẹ+

Nígbà tí mo béèrè pé: “Ìgbà wo lo máa tù mí nínú?”+

83 Nítorí mo dà bí ìgò awọ tí èéfín ti mú kí ó gbẹ,

Àmọ́ mi ò gbàgbé àwọn ìlànà rẹ.+

84 Ọjọ́ mélòó ni kí ìránṣẹ́ rẹ fi dúró?

Ìgbà wo lo máa dá àwọn tó ń ṣe inúnibíni sí mi lẹ́jọ́?+

85 Àwọn tó ń kọjá àyè wọn gbẹ́ kòtò fún mi,

Àwọn tí kì í pa òfin rẹ mọ́.

86 Gbogbo àṣẹ rẹ ṣeé gbẹ́kẹ̀ lé.

Àwọn èèyàn ń ṣe inúnibíni sí mi láìnídìí; ràn mí lọ́wọ́!+

87 Díẹ̀ ló kù kí wọ́n pa mí rẹ́ kúrò láyé,

Àmọ́ mi ò pa àwọn àṣẹ rẹ tì.

88 Mú kí n máa wà láàyè nítorí ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀,

Kí n lè máa pa àwọn ìránnilétí tí o sọ mọ́.

ל [Lámédì]

89 Jèhófà, títí láé

Ni ọ̀rọ̀ rẹ yóò wà ní ọ̀run.+

90 Òtítọ́ rẹ wà láti ìran dé ìran.+

O ti fìdí ayé múlẹ̀ gbọn-in, kó lè máa wà nìṣó.+

91 Nípasẹ̀ ìdájọ́ rẹ ni wọ́n* fi wà títí di òní,

Nítorí ìránṣẹ́ rẹ ni gbogbo wọn.

92 Tí kì í bá ṣe pé mo fẹ́ràn òfin rẹ ni,

Mi ò bá ti ṣègbé nínú ìpọ́njú mi.+

93 Mi ò ní gbàgbé àwọn àṣẹ rẹ láé,

Torí pé nípasẹ̀ wọn lo fi mú kí n wà láàyè.+

94 Tìrẹ ni mo jẹ́; gbà mí sílẹ̀,+

Nítorí pé mo ti wá àwọn àṣẹ rẹ.+

95 Àwọn ẹni burúkú dènà dè mí láti pa mí,

Àmọ́ mò ń fiyè sí àwọn ìránnilétí rẹ.

96 Mo ti rí i pé kò sí ohun tó dáa tí kò kù síbì kan,

Àmọ́ àṣẹ rẹ dára láìkù síbì kan.*

מ [Mémì]

97 Mo mà nífẹ̀ẹ́ òfin rẹ o!+

Àtàárọ̀ ṣúlẹ̀ ni mò ń ronú lé e lórí.*+

98 Àṣẹ rẹ mú kí n gbọ́n ju àwọn ọ̀tá mi lọ,+

Nítorí pé ó wà pẹ̀lú mi títí láé.

99 Mo ní òye tó jinlẹ̀ ju ti gbogbo àwọn olùkọ́ mi,+

Nítorí pé mò ń ronú lórí* àwọn ìránnilétí rẹ.

100 Mò ń fi òye hùwà ju àwọn àgbààgbà lọ,

Nítorí pé mò ń pa àwọn àṣẹ rẹ mọ́.

101 Mi ò rìn ní ọ̀nà ibi èyíkéyìí,+

Kí n lè máa pa ọ̀rọ̀ rẹ mọ́.

102 Mi ò yà kúrò nínú àwọn ìdájọ́ rẹ,

Nítorí o ti kọ́ mi.

103 Àwọn ọ̀rọ̀ rẹ mà dùn mọ́ òkè ẹnu mi o,

Ó dùn ju oyin lọ lẹ́nu mi!+

104 Àwọn àṣẹ rẹ ló mú kí n máa fòye hùwà.+

Ìdí nìyẹn tí mo fi kórìíra gbogbo ọ̀nà èké.+

נ [Núnì]

105 Ọ̀rọ̀ rẹ jẹ́ fìtílà fún ẹsẹ̀ mi

Àti ìmọ́lẹ̀ fún ọ̀nà mi.+

106 Mo ti búra, màá sì mú un ṣẹ,

Kí n lè máa pa àwọn ìdájọ́ rẹ tó jẹ́ òdodo mọ́.

107 A ti fìyà jẹ mí gan-an.+

Jọ̀ọ́ Jèhófà, mú kí n máa wà láàyè bí o ṣe sọ.+

108 Jèhófà, jọ̀ọ́ jẹ́ kí inú rẹ dùn sí ọrẹ ìyìn àtọkànwá mi,*+

Kí o sì kọ́ mi ní àwọn ìdájọ́ rẹ.+

109 Ẹ̀mí mi wà nínú ewu* nígbà gbogbo,

Àmọ́ mi ò gbàgbé òfin rẹ.+

110 Àwọn ẹni burúkú ti dẹ pańpẹ́ dè mí,

Àmọ́ mi ò yà kúrò nínú àwọn àṣẹ rẹ.+

111 Mo fi àwọn ìránnilétí rẹ ṣe ohun ìní mi tí á máa wà títí lọ,*

Nítorí àwọn ni ayọ̀ ọkàn mi.+

112 Mo ti pinnu* láti máa tẹ̀ lé àwọn ìlànà rẹ

Nígbà gbogbo, màá sì ṣe bẹ́ẹ̀ délẹ̀délẹ̀.

ס [Sámékì]

113 Mo kórìíra àwọn aláàbọ̀-ọkàn,*+

Àmọ́ mo nífẹ̀ẹ́ òfin rẹ.+

114 Ìwọ ni ibi ààbò mi àti apata mi,+

Nítorí ọ̀rọ̀ rẹ ni ìrètí mi.*+

115 Ẹ kúrò lọ́dọ̀ mi, ẹ̀yin aṣebi,+

Kí n lè pa àwọn àṣẹ Ọlọ́run mi mọ́.

116 Tì mí lẹ́yìn bí o ti ṣèlérí,*+

Kí n lè máa wà láàyè;

Má ṣe jẹ́ kí ìrètí mi já sí asán.*+

117 Tì mí lẹ́yìn, kí n lè rí ìgbàlà;+

Nígbà náà, èmi yóò máa pọkàn pọ̀ sórí àwọn ìlànà rẹ.+

118 O kọ àwọn tó ń yà kúrò nínú àwọn ìlànà rẹ,+

Nítorí wọ́n jẹ́ onírọ́ àti ẹlẹ́tàn.

119 O kó gbogbo àwọn ẹni burúkú ayé dà nù bíi pàǹtírí.*+

Ìdí nìyẹn tí mo fi nífẹ̀ẹ́ àwọn ìránnilétí rẹ.

120 Ẹ̀rù rẹ mú kí ara* mi máa gbọ̀n;

Mò ń bẹ̀rù àwọn ìdájọ́ rẹ.

ע [Áyìn]

121 Mo ti ṣe ohun tí ó tọ́, tí ó sì jẹ́ òdodo.

Má ṣe fi mí lé ọwọ́ àwọn tó ń ni mí lára!

122 Fi dá ìránṣẹ́ rẹ lójú pé wàá tì í lẹ́yìn;

Kí àwọn tó ń kọjá àyè wọn má ṣe ni mí lára.

123 Ojú mi ti di bàìbàì bí mo ṣe ń dúró de ìgbàlà rẹ+

Àti ìlérí* òdodo rẹ.+

124 Fi ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ hàn sí ìránṣẹ́ rẹ,+

Kí o sì kọ́ mi ní àwọn ìlànà rẹ.+

125 Ìránṣẹ́ rẹ ni mí; fún mi ní òye,+

Kí n lè mọ àwọn ìránnilétí rẹ.

126 Jèhófà, ó ti tó àkókò fún ọ láti gbé ìgbésẹ̀,+

Nítorí wọ́n ti rú òfin rẹ.

127 Ìdí nìyẹn tí mo fi nífẹ̀ẹ́ àwọn àṣẹ rẹ

Ju wúrà, kódà ju wúrà tó dára* lọ.+

128 Nítorí náà, mo gbà pé gbogbo ẹ̀kọ́* tó bá wá látọ̀dọ̀ rẹ tọ̀nà;+

Mo kórìíra gbogbo ọ̀nà èké.+

פ [Péè]

129 Àwọn ìránnilétí rẹ jẹ́ àgbàyanu.

Ìdí nìyẹn tí mo* fi ń kíyè sí wọn.

130 Ṣíṣí ọ̀rọ̀ rẹ payá ń mú ìmọ́lẹ̀ wá,+

Ó ń fún àwọn aláìmọ̀kan ní òye.+

131 Mo la gbogbo ẹnu mi, mo sì mí kanlẹ̀,*

Nítorí pé ọkàn mi ń fà sí àwọn àṣẹ rẹ.+

132 Yíjú sí mi, kí o sì ṣojú rere sí mi,+

Gẹ́gẹ́ bí ìdájọ́ rẹ fún àwọn tó nífẹ̀ẹ́ orúkọ rẹ.+

133 Fi ọ̀rọ̀ rẹ darí ìṣísẹ̀ mi láìséwu;*

Kí aburú kankan má ṣe jọba lórí mi.+

134 Gbà mí* lọ́wọ́ àwọn aninilára,

Màá sì pa àwọn àṣẹ rẹ mọ́.

135 Mú kí ojú rẹ tàn sára* ìránṣẹ́ rẹ,+

Kí o sì kọ́ mi ní àwọn ìlànà rẹ.

136 Omijé ń dà ní ojú mi

Nítorí àwọn èèyàn kò pa òfin rẹ mọ́.+

צ [Sádì]

137 Olódodo ni ọ́, Jèhófà,+

Àwọn ìdájọ́ rẹ sì tọ́.+

138 Àwọn ìránnilétí rẹ jẹ́ òdodo,

Wọ́n sì ṣeé gbára lé pátápátá.

139 Ìtara mi fún ọ gbà mí lọ́kàn,+

Nítorí àwọn ọ̀tá mi ti gbàgbé àwọn ọ̀rọ̀ rẹ.

140 Ọ̀rọ̀ rẹ jẹ́ èyí tí a yọ́ mọ́ dáadáa,+

Ìránṣẹ́ rẹ sì nífẹ̀ẹ́ rẹ̀.+

141 Mi ò já mọ́ nǹkan kan, mo sì jẹ́ ẹni ẹ̀gàn;+

Síbẹ̀, mi ò gbàgbé àwọn àṣẹ rẹ.

142 Òdodo rẹ jẹ́ òdodo ayérayé,+

Òfin rẹ sì jẹ́ òtítọ́.+

143 Bí wàhálà àti ìṣòro tilẹ̀ bá mi,

Síbẹ̀, mo fẹ́ràn àwọn àṣẹ rẹ.

144 Òdodo àwọn ìránnilétí rẹ wà títí láé.

Fún mi ní òye,+ kí n lè máa wà láàyè.

ק [Kófì]

145 Gbogbo ọkàn mi ni mo fi pè ọ́. Dá mi lóhùn, Jèhófà.

Màá pa àwọn ìlànà rẹ mọ́.

146 Mo ké pè ọ́; gbà mí!

Màá pa àwọn ìránnilétí rẹ mọ́.

147 Mo ti jí kí ilẹ̀ tó mọ́,* kí n lè kígbe fún ìrànlọ́wọ́,+

Nítorí àwọn ọ̀rọ̀ rẹ ni ìrètí mi.*

148 Ojú mi là kí àwọn ìṣọ́ òru tó bẹ̀rẹ̀,

Kí n lè ronú lórí* ọ̀rọ̀ rẹ.+

149 Jọ̀wọ́ gbọ́ ohùn mi nítorí ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀.+

Jèhófà, mú kí n máa wà láàyè nítorí ìdájọ́ òdodo rẹ.

150 Àwọn tó ń hu ìwà àìnítìjú* sún mọ́ tòsí;

Wọ́n jìnnà réré sí òfin rẹ.

151 Jèhófà, o wà nítòsí,+

Òtítọ́ sì ni gbogbo àṣẹ rẹ.+

152 Tipẹ́tipẹ́ ni mo ti kọ́ nípa àwọn ìránnilétí rẹ,

Pé o ṣe wọ́n kí wọ́n lè wà títí láé.+

ר [Réṣì]

153 Wo ìyà tó ń jẹ mí, kí o sì gbà mí sílẹ̀,+

Nítorí mi ò gbàgbé òfin rẹ.

154 Gbèjà mi,* kí o sì gbà mí sílẹ̀;+

Mú kí n máa wà láàyè bí o ti ṣèlérí.*

155 Ìgbàlà jìnnà réré sí àwọn ẹni burúkú,

Nítorí wọn kò wá àwọn ìlànà rẹ.+

156 Àánú rẹ pọ̀, Jèhófà.+

Mú kí n máa wà láàyè nítorí ìdájọ́ òdodo rẹ.

157 Àwọn ọ̀tá mi àti àwọn tó ń ṣe inúnibíni sí mi pọ̀;+

Àmọ́ mi ò yà kúrò nínú àwọn ìránnilétí rẹ.

158 Ojú burúkú ni mo fi ń wo àwọn oníbékebèke,

Torí wọn kì í pa ọ̀rọ̀ rẹ mọ́.+

159 Wo bí mo ṣe nífẹ̀ẹ́ àwọn àṣẹ rẹ!

Jèhófà, mú kí n máa wà láàyè nítorí ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀.+

160 Òtítọ́ ni kókó inú ọ̀rọ̀ rẹ,+

Gbogbo ìdájọ́ rẹ tí ó jẹ́ òdodo sì wà títí láé.

ש [Sínì] tàbí [Ṣínì]

161 Àwọn olórí ń ṣe inúnibíni sí mi+ láìnídìí,

Àmọ́ ìbẹ̀rù ọ̀rọ̀ rẹ wà lọ́kàn mi.+

162 Ọ̀rọ̀ rẹ ń mú inú mi dùn,+

Bí ẹni tó rí ẹrù púpọ̀ kó lójú ogun.

163 Mo kórìíra irọ́, mo kórìíra rẹ̀ gidigidi,+

Mo nífẹ̀ẹ́ òfin rẹ.+

164 Ìgbà méje lóòjọ́ ni mò ń yìn ọ́

Nítorí àwọn ìdájọ́ rẹ tí ó jẹ́ òdodo.

165 Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àlàáfíà jẹ́ ti àwọn tó nífẹ̀ẹ́ òfin rẹ;+

Kò sí ohun tó lè mú wọn kọsẹ̀.*

166 Mò ń retí àwọn iṣẹ́ ìgbàlà rẹ, Jèhófà,

Mo sì ń pa àwọn àṣẹ rẹ mọ́.

167 Mò* ń pa àwọn ìránnilétí rẹ mọ́,

Mo sì nífẹ̀ẹ́ wọn púpọ̀.+

168 Mò ń pa àwọn àṣẹ àti àwọn ìránnilétí rẹ mọ́,

Nítorí o mọ gbogbo ohun tí mò ń ṣe.+

ת [Tọ́ọ̀]

169 Kí igbe mi fún ìrànlọ́wọ́ dé ọ̀dọ̀ rẹ, Jèhófà.+

Fún mi ní òye nípasẹ̀ ọ̀rọ̀ rẹ.+

170 Kí ìbéèrè mi fún ojú rere wá síwájú rẹ.

Gbà mí bí o ti ṣèlérí.*

171 Kí ìyìn kún ẹnu mi,*+

Nítorí o ti kọ́ mi ní àwọn ìlànà rẹ.

172 Kí ahọ́n mi máa fi ọ̀rọ̀ rẹ kọrin,+

Nítorí gbogbo àṣẹ rẹ jẹ́ òdodo.

173 Kí ọwọ́ rẹ ṣe tán láti ràn mí lọ́wọ́,+

Nítorí mo ti pinnu pé màá máa pa àwọn àṣẹ rẹ mọ́.+

174 Ọkàn mi ń fà sí ìgbàlà rẹ, Jèhófà,

Mo sì fẹ́ràn òfin rẹ.+

175 Jẹ́ kí n* máa wà láàyè, kí n lè máa yìn ọ́;+

Kí àwọn ìdájọ́ rẹ máa ràn mí lọ́wọ́.

176 Mo ti ṣìnà bí àgùntàn tó sọ nù.+ Wá ìránṣẹ́ rẹ,

Nítorí mi ò gbàgbé àwọn àṣẹ rẹ.+

Orin Ìgòkè.*

120 Mo ké pe Jèhófà nínú wàhálà mi,+

Ó sì dá mi lóhùn.+

 2 Jèhófà, gbà mí* lọ́wọ́ ètè tó ń parọ́

Àti lọ́wọ́ ahọ́n ẹ̀tàn.

 3 Ṣé o mọ ohun tí Ó máa ṣe sí ọ, ṣé o mọ ìyà tí Ó máa fi jẹ ọ́,*

Ìwọ ahọ́n ẹ̀tàn?+

 4 Yóò lo àwọn ọfà mímú+ jagunjagun

Àti ẹyin iná+ àwọn igi wíwẹ́.

 5 Mo gbé, nítorí mo jẹ́ àjèjì ní Méṣékì!+

Mò ń gbé láàárín àwọn àgọ́ Kídárì.+

 6 Mo* ti ń gbé tipẹ́tipẹ́

Pẹ̀lú àwọn tó kórìíra àlàáfíà.+

 7 Àlàáfíà ni èmi ń fẹ́, àmọ́ nígbà tí mo bá sọ̀rọ̀,

Ogun ni wọ́n ń fẹ́.

Orin Ìgòkè.

121 Mo gbé ojú mi sókè sí àwọn òkè.+

Ibo ni ìrànlọ́wọ́ mi yóò ti wá?

2 Ọ̀dọ̀ Jèhófà ni ìrànlọ́wọ́ mi ti ń wá,+

Aṣẹ̀dá ọ̀run àti ayé.

3 Kò ní jẹ́ kí ẹsẹ̀ rẹ yọ̀.*+

Ẹni tó ń ṣọ́ ọ kò ní tòògbé láé.

4 Wò ó! Ẹni tó ń ṣọ́ Ísírẹ́lì kì í tòògbé,

Bẹ́ẹ̀ ni kì í sùn.+

5 Jèhófà ń ṣọ́ ọ.

Jèhófà ni ibòji+ tó wà ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ.+

6 Oòrùn kò ní pa ọ́ lára ní ọ̀sán,+

Tàbí òṣùpá ní òru.+

7 Jèhófà yóò máa ṣọ́ ọ kí jàǹbá kankan má ṣe ọ́.+

Yóò máa ṣọ́ ẹ̀mí* rẹ.+

8 Jèhófà yóò máa ṣọ́ ọ nínú gbogbo ohun tí o bá ń ṣe*

Láti ìsinsìnyí lọ àti títí láé.

Orin Ìgòkè. Ti Dáfídì.

122 Mo yọ̀ nígbà tí wọ́n sọ fún mi pé:

“Jẹ́ ká lọ sí ilé Jèhófà.”+

2 Ní báyìí, ẹsẹ̀ wa dúró

Ní àwọn ẹnubodè rẹ, ìwọ Jerúsálẹ́mù.+

3 A kọ́ Jerúsálẹ́mù bí ìlú,

Ó so pọ̀ mọ́ra.+

4 Àwọn ẹ̀yà ti lọ síbẹ̀,

Àwọn ẹ̀yà Jáà,*

Kí wọ́n lè fi ọpẹ́ fún orúkọ Jèhófà,

Gẹ́gẹ́ bí ìrántí fún Ísírẹ́lì.+

5 Nítorí ibẹ̀ la gbé àwọn ìtẹ́ ìdájọ́ kalẹ̀ sí,+

Àwọn ìtẹ́ ilé Dáfídì.+

6 Ẹ gbàdúrà pé kí Jerúsálẹ́mù ní àlàáfíà.+

Àwọn tó nífẹ̀ẹ́ rẹ yóò wà láìséwu, ìwọ ìlú.

7 Kí àlàáfíà máa wà nínú àwọn odi rẹ,*

Kí ààbò sì wà nínú àwọn ilé gogoro rẹ tó láàbò.

8 Nítorí àwọn arákùnrin mi àti àwọn ọ̀rẹ́ mi, màá sọ pé:

“Kí àlàáfíà wà nínú rẹ.”

9 Nítorí ilé Jèhófà Ọlọ́run wa,+

Màá wá ire fún ọ.

Orin Ìgòkè.

123 Ìwọ ni mo gbé ojú mi sókè sí,+

Ìwọ tí o gúnwà ní ọ̀run.

2 Bí ojú àwọn ìránṣẹ́ ṣe ń wo ọwọ́ ọ̀gá wọn

Àti bí ojú ìránṣẹ́bìnrin ṣe ń wo ọwọ́ ọ̀gá rẹ̀ obìnrin,

Bẹ́ẹ̀ ni ojú wa ń wo Jèhófà Ọlọ́run wa,+

Títí á fi ṣojú rere sí wa.+

3 Ṣojú rere sí wa, Jèhófà, ṣojú rere sí wa,

Nítorí wọ́n ti kàn wá lábùkù dé góńgó.+

4 Àwọn ajọra-ẹni-lójú ti fi wá ṣẹ̀sín dé góńgó,*

Àwọn agbéraga sì ti kàn wá lábùkù gidigidi.

Orin Ìgòkè. Ti Dáfídì.

124 “Ká ní Jèhófà ò wà pẹ̀lú wa ni”+

—Kí Ísírẹ́lì sọ pé—

2 “Ká ní Jèhófà ò wà pẹ̀lú wa ni+

Nígbà tí àwọn èèyàn dìde láti bá wa jà,+

3 Wọn ì bá ti gbé wa mì láàyè+

Nígbà tí inú wọn ń ru sí wa.+

4 Omi ì bá ti gbé wa lọ,

Ọ̀gbàrá ì bá ti ṣàn kọjá lórí wa.*+

5 Omi tó ń ru gùdù ì bá ti bò wá* mọ́lẹ̀.

6 Ìyìn ni fún Jèhófà,

Torí kò fi wá ṣe ẹran ìjẹ fún eyín wọn.

7 A* dà bí ẹyẹ tó bọ́

Nínú pańpẹ́ ọdẹ;+

Pańpẹ́ náà ṣẹ́,

A sì bọ́.+

8 Ìrànlọ́wọ́ wa wà nínú orúkọ Jèhófà,+

Aṣẹ̀dá ọ̀run àti ayé.”

Orin Ìgòkè.

125 Àwọn tó gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà+

Dà bí Òkè Síónì, tí kò ṣeé mì,

Àmọ́ tí ó wà títí láé.+

 2 Bí àwọn òkè ṣe yí Jerúsálẹ́mù ká,+

Bẹ́ẹ̀ ni Jèhófà yí àwọn èèyàn rẹ̀ ká+

Láti ìsinsìnyí lọ àti títí láé.

 3 Ọ̀pá àṣẹ ìwà burúkú kò ní máa wà lórí ilẹ̀ tí a pín fún àwọn olódodo,+

Kí àwọn olódodo má bàa bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe* ohun tí kò tọ́.+

 4 Jèhófà, ṣe rere sí àwọn ẹni rere,+

Sí àwọn tí ọkàn wọn dúró ṣinṣin.+

 5 Ní ti àwọn tó yà sí ọ̀nà àìtọ́,

Jèhófà yóò mú wọn kúrò pẹ̀lú àwọn aṣebi.+

Kí àlàáfíà wà ní Ísírẹ́lì.

Orin Ìgòkè.

126 Nígbà tí Jèhófà kó àwọn èèyàn Síónì tó wà lóko ẹrú pa dà,+

A rò pé à ń lá àlá ni.

 2 Ní àkókò yẹn, ẹ̀rín kún ẹnu wa,

Ahọ́n wa sì ń kígbe ayọ̀.+

Ní àkókò yẹn, wọ́n ń sọ láàárín àwọn orílẹ̀-èdè pé:

“Jèhófà ti ṣe àwọn ohun ńlá fún wọn.”+

 3 Jèhófà ti ṣe àwọn ohun ńlá fún wa,+

Ayọ̀ wa sì kún.

 4 Jèhófà, jọ̀wọ́ kó* àwọn èèyàn wa tó wà lóko ẹrú pa dà,

Bí ìṣàn omi tó wà ní Négébù.*

 5 Àwọn tó ń fi omijé fúnrúgbìn

Yóò fi igbe ayọ̀ kórè.

 6 Ẹni tó ń jáde, bó tilẹ̀ ń sunkún,

Tó gbé àpò irúgbìn rẹ̀ dání,

Ó dájú pé ó máa pa dà pẹ̀lú igbe ayọ̀,+

Bó ṣe ń gbé àwọn ìtí rẹ̀ wọlé.+

Orin Ìgòkè. Ti Sólómọ́nì.

127 Bí Jèhófà ò bá kọ́ ilé,

Lásán ni àwọn tó ń kọ́ ọ ṣiṣẹ́ kára lórí rẹ̀.+

Bí Jèhófà ò bá ṣọ́ ìlú,+

Lásán ni ẹ̀ṣọ́ wà lójúfò.

2 Lásán lẹ̀ ń dìde ní kùtùkùtù,

Tí ẹ̀ ń pẹ́ kí ẹ tó sùn,

Tí ẹ sì ń fi gbogbo agbára ṣiṣẹ́ kí ẹ lè rí oúnjẹ,

Torí Ọlọ́run ń pèsè fún àwọn tó fẹ́ràn, ó sì ń jẹ́ kí wọ́n rí oorun sùn.+

3 Wò ó! Àwọn ọmọ* jẹ́ ogún láti ọ̀dọ̀ Jèhófà;+

Èso ikùn* jẹ́ èrè.+

4 Bí ọfà ní ọwọ́ alágbára ọkùnrin,

Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọmọ téèyàn bí nígbà ọ̀dọ́.+

5 Aláyọ̀ ni ọkùnrin tó fi wọ́n kún apó rẹ̀.+

Ojú kò ní tì wọ́n,

Nítorí wọ́n á bá àwọn ọ̀tá sọ̀rọ̀ ní ẹnubodè ìlú.

Orin Ìgòkè.

128 Aláyọ̀ ni gbogbo ẹni tó bẹ̀rù Jèhófà,+

Tó ń rìn ní àwọn ọ̀nà Rẹ̀.+

2 Wàá jẹ ohun tí ọwọ́ rẹ ṣiṣẹ́ kára láti mú jáde.

Wàá láyọ̀, wàá sì láásìkí.+

3 Ìyàwó rẹ yóò dà bí igi àjàrà tó ń so nínú ilé rẹ;+

Àwọn ọmọ rẹ yóò dà bí àwọn ẹ̀ka tó ṣẹ̀ṣẹ̀ yọ lára igi ólífì, wọ́n á yí tábìlì rẹ ká.

4 Wò ó! Bí ọkùnrin tó bẹ̀rù Jèhófà

Ṣe máa rí ìbùkún gbà nìyẹn.+

5 Jèhófà yóò bù kún ọ láti Síónì.

Kí aásìkí Jerúsálẹ́mù ṣojú rẹ ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ,+

6 Kí o sì rí àwọn ọmọ ọmọ rẹ.

Kí àlàáfíà wà ní Ísírẹ́lì.

Orin Ìgòkè.

129 “Láti ìgbà èwe mi ni wọ́n ti ń gbógun tì mí”+

—Kí Ísírẹ́lì sọ pé—

2 “Láti ìgbà èwe mi ni wọ́n ti ń gbógun tì mí;+

Àmọ́, wọn kò ṣẹ́gun mi.+

3 Àwọn tó ń túlẹ̀ ti túlẹ̀ kọjá lórí ẹ̀yìn mi;+

Wọ́n ti mú kí àwọn poro* wọn gùn.”

4 Àmọ́ olódodo ni Jèhófà;+

Ó ti gé okùn àwọn ẹni burúkú.+

5 Ojú á tì wọ́n, wọ́n á sì sá pa dà nínú ìtìjú,

Gbogbo àwọn tó kórìíra Síónì.+

6 Wọ́n á dà bíi koríko orí òrùlé

Tó ti rọ kí a tó fà á tu,

7 Tí kò lè kún ọwọ́ ẹni tó ń kórè,

Tàbí apá ẹni tó ń kó ìtí jọ.

8 Àwọn tó ń kọjá lọ kò ní sọ pé:

“Kí ìbùkún Jèhófà wà lórí yín;

A súre fún yín ní orúkọ Jèhófà.”

Orin Ìgòkè.

130 Láti inú ibú ni mo ti ké pè ọ́, Jèhófà.+

2 Jèhófà, gbọ́ ohùn mi.

Kí etí rẹ ṣí sí ẹ̀bẹ̀ mi fún ìrànlọ́wọ́.

3 Jáà,* tó bá jẹ́ pé àṣìṣe lò ń wò,*

Jèhófà, ta ló lè dúró?+

4 Nítorí ìdáríjì tòótọ́ wà lọ́dọ̀ rẹ,+

Kí a lè máa bọ̀wọ̀ fún ọ.*+

5 Mo gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, gbogbo ara* mi gbẹ́kẹ̀ lé e;

Mò ń dúró de ọ̀rọ̀ rẹ̀.

6 Mò* ń retí Jèhófà,+

Ju bí àwọn olùṣọ́ ṣe ń retí pé kí ilẹ̀ mọ́,+

Àní, ju bí àwọn olùṣọ́ ṣe ń retí pé kí ilẹ̀ mọ́.

7 Kí Ísírẹ́lì máa dúró de Jèhófà,

Nítorí ìfẹ́ Jèhófà kì í yẹ̀,+

Ó sì ní agbára ńlá tó lè fi rani pa dà.

8 Yóò ra Ísírẹ́lì pa dà nínú gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ wọn.

Orin Ìgòkè. Ti Dáfídì.

131 Jèhófà, mi* ò gbéra ga,

Bẹ́ẹ̀ ni ojú mi ò ga;+

Bẹ́ẹ̀ ni mi ò máa lé nǹkan ńláńlá,+

Tàbí àwọn nǹkan tó kọjá agbára mi.

2 Àmọ́, mo ti tu ọkàn* mi lára, mo sì ti mú kó pa rọ́rọ́ +

Bí ọmọ tí a ti gba ọmú lẹ́nu rẹ̀, tó wà lọ́dọ̀ ìyá rẹ̀;

Mo* ní ìtẹ́lọ́rùn bí ọmọ tí a ti gba ọmú lẹ́nu rẹ̀.

3 Kí Ísírẹ́lì dúró de Jèhófà+

Láti ìsinsìnyí lọ àti títí láé.

Orin Ìgòkè.

132 Jèhófà, jọ̀wọ́ rántí Dáfídì

Àti gbogbo ìyà tó jẹ;+

2 Bó ṣe búra fún Jèhófà,

Bó ṣe jẹ́jẹ̀ẹ́ fún Alágbára Jékọ́bù pé:+

3 “Mi ò ní wọnú àgọ́ mi, àní ilé mi.+

Mi ò ní dùbúlẹ̀ lórí àga tìmùtìmù mi, àní ibùsùn mi;

4 Mi ò ní jẹ́ kí oorun kun ojú mi,

Mi ò sì ní jẹ́ kí ìpéǹpéjú mi tòògbé

5 Títí màá fi rí àyè kan fún Jèhófà,

Ibùgbé tó dáa* fún Alágbára Jékọ́bù.”+

6 Wò ó! A gbọ́ nípa rẹ̀ ní Éfúrátà;+

A rí i nínú igbó kìjikìji.+

7 Ẹ jẹ́ ká wá sínú ibùgbé rẹ̀;*+

Ká forí balẹ̀ níbi àpótí ìtìsẹ̀ rẹ̀.+

8 Dìde, Jèhófà, wá sí ibi ìsinmi rẹ,+

Ìwọ àti Àpótí agbára rẹ.+

9 Kí àwọn àlùfáà rẹ gbé òdodo wọ̀,

Kí àwọn ẹni ìdúróṣinṣin rẹ sì máa kígbe ayọ̀.

10 Nítorí Dáfídì ìránṣẹ́ rẹ,

Má ṣe kọ ẹni àmì òróró rẹ sílẹ̀.*+

11 Jèhófà ti búra fún Dáfídì,

Ó dájú pé kò ní ṣàìmú ọ̀rọ̀ rẹ̀ ṣẹ pé:

“Ọ̀kan lára ọmọ* rẹ

Ni màá gbé gorí ìtẹ́ rẹ.+

12 Tí àwọn ọmọ rẹ bá pa májẹ̀mú mi mọ́

Àti àwọn ìránnilétí mi tí mo kọ́ wọn,+

Àwọn ọmọ tiwọn náà

Yóò jókòó sórí ìtẹ́ rẹ títí láé.”+

13 Nítorí Jèhófà ti yan Síónì;+

Ó fẹ́ kó jẹ́ ibùgbé rẹ̀, ó ní:+

14 “Ibi ìsinmi mi títí láé nìyí;

Ibí ni màá máa gbé,+ nítorí ohun tí mo fẹ́ nìyẹn.

15 Màá fi ọ̀pọ̀ oúnjẹ kún ibẹ̀;

Màá fi oúnjẹ tẹ́ àwọn aláìní ibẹ̀ lọ́rùn.+

16 Màá gbé ìgbàlà wọ àwọn àlùfáà rẹ̀,+

Àwọn adúróṣinṣin rẹ̀ yóò sì kígbe ayọ̀.+

17 Màá mú kí agbára Dáfídì pọ̀ sí i* níbẹ̀.

Mo ti ṣètò fìtílà fún ẹni àmì òróró mi.+

18 Màá gbé ìtìjú wọ àwọn ọ̀tá rẹ̀,

Àmọ́ adé* orí rẹ̀ yóò máa gbilẹ̀.”+

Orin Ìgòkè. Ti Dáfídì.

133 Wò ó! Ó mà dára o, ó mà dùn o

Pé kí àwọn ará máa gbé pọ̀ ní ìṣọ̀kan!+

2 Ó dà bí òróró dáradára tí a dà sí orí,+

Tó ń ṣàn sára irùngbọ̀n,

Irùngbọ̀n Áárónì,+

Tó sì ń ṣàn sí ọrùn aṣọ rẹ̀.

3 Ó dà bí ìrì Hámónì+

Tó ń sẹ̀ sórí àwọn òkè Síónì.+

Ibẹ̀ ni Jèhófà ti pàṣẹ ìbùkún rẹ̀,

Ìyè àìnípẹ̀kun.

Orin Ìgòkè.

134 Ẹ yin Jèhófà,

Gbogbo ẹ̀yin ìránṣẹ́ Jèhófà,+

Ẹ̀yin tó ń ṣiṣẹ́ nínú ilé Jèhófà ní òròòru.+

2 Ẹ gbé ọwọ́ yín sókè+ nínú ìjẹ́mímọ́,*

Kí ẹ sì yin Jèhófà.

3 Kí Jèhófà, Aṣẹ̀dá ọ̀run àti ayé,

Bù kún ọ láti Síónì.

135 Ẹ yin Jáà!*

Ẹ yin orúkọ Jèhófà;

Ẹ mú ìyìn wá, ẹ̀yin ìránṣẹ́ Jèhófà,+

2 Ẹ̀yin tó ń ṣiṣẹ́ nínú ilé Jèhófà,

Nínú àwọn àgbàlá ilé Ọlọ́run wa.+

3 Ẹ yin Jáà, nítorí Jèhófà jẹ́ ẹni rere.+

Ẹ kọ orin ìyìn* sí orúkọ rẹ̀, nítorí ó dára.

4 Jáà ti yan Jékọ́bù fún ara rẹ̀,

Ó ti yan Ísírẹ́lì ṣe ohun ìní rẹ̀ pàtàkì.*+

5 Mo mọ̀ dáadáa pé Jèhófà tóbi;

Olúwa wa ju gbogbo ọlọ́run yòókù lọ.+

6 Jèhófà ń ṣe gbogbo ohun tó bá fẹ́+

Ní ọ̀run àti ní ayé, nínú òkun àti nínú gbogbo ibú omi.

7 Ó ń mú kí ìkùukùu* ròkè láti ìkángun ayé;

Ó ń ṣe mànàmáná* fún òjò;

Ó ń mú ẹ̀fúùfù jáde látinú àwọn ilé ìṣúra rẹ̀.+

8 Ó pa àwọn àkọ́bí Íjíbítì,

Àti èèyàn àti ẹranko.+

9 Ó rán àwọn iṣẹ́ àmì àti iṣẹ́ ìyanu sáàárín rẹ, ìwọ Íjíbítì,+

Sí Fáráò àti sí gbogbo ìránṣẹ́ rẹ̀.+

10 Ó pa ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè+ run,

Ó sì pa àwọn ọba alágbára+

11 —Síhónì ọba àwọn Ámórì,+

Ógù ọba Báṣánì+

Àti gbogbo àwọn ìjọba Kénáánì.

12 Ó fi ilẹ̀ wọn ṣe ogún,

Ó fi ṣe ogún fún Ísírẹ́lì, àwọn èèyàn rẹ̀.+

13 Jèhófà, orúkọ rẹ wà títí láé.

Jèhófà, òkìkí rẹ yóò máa kàn* láti ìran dé ìran.+

14 Nítorí Jèhófà yóò gbèjà àwọn èèyàn rẹ̀,*+

Yóò sì ṣàánú* àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀.+

15 Àwọn òrìṣà orílẹ̀-èdè jẹ́ fàdákà àti wúrà,

Iṣẹ́ ọwọ́ èèyàn.+

16 Wọ́n ní ẹnu, àmọ́ wọn ò lè sọ̀rọ̀;+

Wọ́n ní ojú, àmọ́ wọn ò lè ríran;

17 Wọ́n ní etí, àmọ́ wọn ò lè gbọ́ràn.

Kò sí èémí kankan ní ẹnu wọn.+

18 Àwọn tó ń ṣe wọ́n yóò dà bíi wọn gẹ́lẹ́,+

Bẹ́ẹ̀ ló sì ṣe máa rí fún gbogbo àwọn tó gbẹ́kẹ̀ lé wọn.+

19 Ilé Ísírẹ́lì, ẹ yin Jèhófà.

Ilé Áárónì, ẹ yin Jèhófà.

20 Ilé Léfì, ẹ yin Jèhófà.+

Ẹ̀yin tí ẹ bẹ̀rù Jèhófà, ẹ yin Jèhófà.

21 Ìyìn ni fún Jèhófà láti Síónì,+

Ẹni tó ń gbé ní Jerúsálẹ́mù.+

Ẹ yin Jáà!+

136 Ẹ fi ọpẹ́ fún Jèhófà, nítorí ó jẹ́ ẹni rere;+

Ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí láé.+

2 Ẹ fi ọpẹ́ fún Ọlọ́run àwọn ọlọ́run,+

Nítorí ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí láé.

3 Ẹ fi ọpẹ́ fún Olúwa àwọn olúwa,

Nítorí ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí láé.

4 Òun nìkan ló ń ṣe àwọn ohun àgbàyanu,+

Nítorí ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí láé.+

5 Ó fi ọgbọ́n* dá àwọn ọ̀run,+

Nítorí ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí láé.

6 Ó tẹ́ ayé sórí omi,+

Nítorí ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí láé.

7 Ó dá àwọn ìmọ́lẹ̀ ńlá,+

Nítorí ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí láé.

8 Oòrùn láti máa jọba lórí ọ̀sán,+

Nítorí ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí láé.

9 Òṣùpá àti àwọn ìràwọ̀ láti máa jọba lórí òru,+

Nítorí ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí láé.

10 Ó pa àwọn àkọ́bí Íjíbítì,+

Nítorí ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí láé.

11 Ó mú Ísírẹ́lì jáde kúrò láàárín wọn,+

Nítorí ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí láé.

12 Pẹ̀lú ọwọ́ agbára+ àti apá tó nà jáde,

Nítorí ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí láé.

13 Ó pín Òkun Pupa sí méjì,*+

Nítorí ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí láé.

14 Ó mú kí Ísírẹ́lì gba àárín rẹ̀ kọjá,+

Nítorí ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí láé.

15 Ó gbọn Fáráò àti àwọn ọmọ ogun rẹ̀ sínú Òkun Pupa,+

Nítorí ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí láé.

16 Ó mú àwọn èèyàn rẹ̀ gba inú aginjù kọjá,+

Nítorí ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí láé.

17 Ó pa àwọn ọba ńlá,+

Nítorí ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí láé.

18 Ó pa àwọn ọba alágbára,

Nítorí ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí láé.

19 Síhónì+ ọba àwọn Ámórì,

Nítorí ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí láé

20 Àti Ógù+ ọba Báṣánì,

Nítorí ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí láé.

21 Ó fi ilẹ̀ wọn ṣe ogún,+

Nítorí ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí láé.

22 Ó fi ṣe ogún fún Ísírẹ́lì ìránṣẹ́ rẹ̀,

Nítorí ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí láé.

23 Ó rántí wa nígbà tí wọ́n rẹ̀ wá sílẹ̀,+

Nítorí ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí láé.+

24 Ó ń gbà wá sílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá wa,+

Nítorí ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí láé.

25 Ó ń fún gbogbo ohun alààyè* ní oúnjẹ,+

Nítorí ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí láé.

26 Ẹ fi ọpẹ́ fún Ọlọ́run ọ̀run,

Nítorí ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí láé.

137 Létí àwọn odò Bábílónì,+ ibẹ̀ la jókòó sí.

A sunkún nígbà tí a rántí Síónì.+

2 Orí àwọn igi pọ́pílà tó wà láàárín rẹ̀*

Ni a gbé àwọn háàpù wa kọ́.+

3 Ibẹ̀ ni àwọn tó mú wa lẹ́rú ti ní ká kọrin,+

Àwọn tó ń fi wá ṣẹ̀sín fẹ́ ká dá àwọn lára yá, wọ́n ní:

“Ẹ kọ ọ̀kan lára àwọn orin Síónì fún wa.”

4 Báwo la ó ṣe kọ orin Jèhófà

Ní ilẹ̀ àjèjì?

5 Tí mo bá gbàgbé rẹ, ìwọ Jerúsálẹ́mù,

Kí ọwọ́ ọ̀tún mi gbàgbé ohun tó mọ̀ ọ́n ṣe.*+

6 Kí ahọ́n mi lẹ̀ mọ́ òkè ẹnu mi

Tí mi ò bá rántí rẹ,

Tí mi ò bá gbé Jerúsálẹ́mù ga kọjá

Olórí ohun tó ń fún mi láyọ̀.+

7 Jèhófà, jọ̀wọ́ rántí

Ohun tí àwọn ọmọ Édómù sọ lọ́jọ́ tí Jerúsálẹ́mù ṣubú, wọ́n ní:

“Ẹ wó o palẹ̀! Ẹ wó o palẹ̀ dé ìpìlẹ̀ rẹ̀!”+

8 Ìwọ ọmọbìnrin Bábílónì, tí kò ní pẹ́ di ahoro,+

Aláyọ̀ ni ẹni tó máa san ọ́ lẹ́san

Lórí ohun tí o ṣe sí wa.+

9 Aláyọ̀ ni ẹni tó máa gba àwọn ọmọ rẹ lọ́wọ́ rẹ,

Tí á sì là wọ́n mọ́ àpáta.+

Ti Dáfídì.

138 Màá fi gbogbo ọkàn mi yìn ọ́.+

Níṣojú àwọn ọlọ́run mìíràn,

Màá kọ orin ìyìn.*

2 Màá forí balẹ̀ ní ìdojúkọ tẹ́ńpìlì mímọ́ rẹ,*+

Màá sì yin orúkọ rẹ,+

Nítorí ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ àti òtítọ́ rẹ.

Torí o ti gbé ọ̀rọ̀ rẹ àti orúkọ rẹ ga ju gbogbo nǹkan míì lọ.*

3 Ní ọjọ́ tí mo pè, o dá mi lóhùn;+

O mú kí n* nígboyà, o sì mú kí n lágbára.+

4 Gbogbo ọba ayé yóò yìn ọ́, Jèhófà,+

Nítorí wọ́n á ti gbọ́ àwọn ìlérí tí o ṣe.

5 Wọ́n á máa fi àwọn ọ̀nà Jèhófà kọrin,

Nítorí pé ògo Jèhófà pọ̀.+

6 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Jèhófà ga, ó ń kíyè sí àwọn onírẹ̀lẹ̀,+

Àmọ́, ó jìnnà sí àwọn agbéraga.+

7 Bí mo bá tiẹ̀ ń rìn nínú ewu, wàá dá ẹ̀mí mi sí.+

O na ọwọ́ rẹ sórí àwọn ọ̀tá mi tó ń bínú;

Ọwọ́ ọ̀tún rẹ yóò gbà mí là.

8 Jèhófà yóò mú gbogbo ohun tó ní lọ́kàn fún mi ṣẹ.

Jèhófà, ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ wà títí láé;+

Má ṣe pa àwọn iṣẹ́ ọwọ́ rẹ tì.+

Fún olùdarí. Ti Dáfídì. Orin.

139 Jèhófà, o ti yẹ̀ mí wò látòkè délẹ̀, o sì mọ̀ mí.+

2 O mọ ìgbà tí mo bá jókòó àti ìgbà tí mo bá dìde.+

Láti ibi tó jìnnà réré, o mọ ohun tí mò ń rò.+

3 Ò ń kíyè sí* mi nígbà tí mo bá ń rìnrìn àjò àti nígbà tí mo bá dùbúlẹ̀;

Gbogbo àwọn ọ̀nà mi ò ṣàjèjì sí ọ.+

4 Kí n tó sọ̀rọ̀ jáde lẹ́nu,

Wò ó, Jèhófà, o ti mọ gbogbo ohun tí mo fẹ́ sọ.+

5 Lẹ́yìn mi àti níwájú mi, o yí mi ká;

O sì gbé ọwọ́ rẹ lé mi.

6 Irú ìmọ̀ bẹ́ẹ̀ kọjá òye mi.*

Ó kọjá ohun tí ọwọ́ mi lè tẹ̀.*+

7 Ibo ni mo lè sá sí tí màá fi bọ́ lọ́wọ́ ẹ̀mí rẹ,

Ibo ni mo sì lè sá lọ kí ojú rẹ má bàa tó mi?+

8 Tí mo bá lọ sọ́run, wàá wà níbẹ̀,

Tí mo bá sì tẹ́ ibùsùn mi sínú Isà Òkú,* wò ó! wàá ti wà níbẹ̀.+

9 Tí mo bá fi ìyẹ́ apá ọ̀yẹ̀ fò lọ,

Kí n lè máa gbé létí òkun tó jìnnà jù lọ,

10 Kódà, ọwọ́ rẹ yóò darí mi níbẹ̀,

Ọwọ́ ọ̀tún rẹ yóò sì dì mí mú.+

11 Tí mo bá sọ pé: “Dájúdájú, òkùnkùn yóò fi mí pa mọ́!”

Nígbà náà, òkùnkùn tó yí mi ká yóò di ìmọ́lẹ̀.

12 Kódà, òkùnkùn náà kò ní ṣú jù fún ọ,

Ṣe ni òru yóò mọ́lẹ̀ bí ọ̀sán;+

Ìkan náà ni òkùnkùn àti ìmọ́lẹ̀ lójú rẹ.+

13 Ìwọ lo ṣe àwọn kíndìnrín mi;

O yà mí sọ́tọ̀* ní inú ìyá mi.+

14 Mo yìn ọ́ nítorí pé lọ́nà tó ń bani lẹ́rù ni o ṣẹ̀dá mi tìyanutìyanu.+

Àgbàyanu ni àwọn iṣẹ́ rẹ,+

Mo* mọ èyí dáadáa.

15 Àwọn egungun mi ò pa mọ́ fún ọ

Nígbà tí o ṣẹ̀dá mi ní ìkọ̀kọ̀,

Nígbà tí o hun mí ní ìsàlẹ̀ ayé.+

16 Kódà, ojú rẹ rí mi nígbà tí mo ṣì wà nínú ikùn;*

Gbogbo àwọn ẹ̀yà rẹ̀ wà lákọsílẹ̀ nínú ìwé rẹ

Ní ti àwọn ọjọ́ tí o ṣẹ̀dá wọn,

Kí ìkankan lára wọn tó wà.

17 Lójú tèmi, àwọn ìrònú rẹ mà ṣeyebíye o!+

Ọlọ́run, àròpọ̀ iye wọn mà pọ̀ o!+

18 Tí mo bá ní kí n máa kà wọ́n, wọ́n pọ̀ ju iyanrìn lọ.+

Nígbà tí mo jí, mo ṣì wà pẹ̀lú rẹ.*+

19 Ọlọ́run, ká ní o bá pa ẹni burúkú!+

Nígbà náà, àwọn oníwà ipá* yóò kúrò lọ́dọ̀ mi,

20 Àwọn tó ń sọ̀rọ̀ rẹ pẹ̀lú èrò ibi lọ́kàn;*

Àwọn ni ọ̀tá rẹ tí wọ́n ń lo orúkọ rẹ lọ́nà tí kò ní láárí.+

21 Mo kórìíra àwọn tó kórìíra rẹ, Jèhófà,+

Mi ò sì nífẹ̀ẹ́ àwọn tó ń dìtẹ̀ sí ọ.+

22 Mo kórìíra wọn gan-an;+

Wọ́n ti di ọ̀tá paraku sí mi.

23 Yẹ̀ mí wò látòkè délẹ̀, Ọlọ́run, kí o sì mọ ọkàn mi.+

Ṣàyẹ̀wò mi, kí o sì mọ àwọn ohun tó ń gbé mi lọ́kàn sókè.*+

24 Wò ó bóyá ìwà burúkú kankan wà nínú mi,+

Kí o sì darí mi+ sí ọ̀nà ayérayé.

Fún olùdarí. Orin Dáfídì.

140 Jèhófà, gbà mí lọ́wọ́ àwọn aṣebi;

Dáàbò bò mí lọ́wọ́ àwọn oníwà ipá,+

2 Àwọn tó ń gbèrò ibi nínú ọkàn wọn,+

Tí wọ́n sì ń dá ìjà sílẹ̀ látàárọ̀ ṣúlẹ̀.

3 Wọ́n pọ́n ahọ́n wọn bíi ti ejò;+

Oró paramọ́lẹ̀ wà lábẹ́ ètè wọn.+ (Sélà)

4 Jèhófà, dáàbò bò mí lọ́wọ́ ẹni burúkú;+

Máa ṣọ́ mi lọ́wọ́ àwọn oníwà ipá,

Àwọn tó ń gbèrò láti mú kí n yọ̀ ṣubú.

5 Àwọn agbéraga dẹ pańpẹ́ pa mọ́ dè mí;

Wọ́n fi okùn ta àwọ̀n sẹ́gbẹ̀ẹ́ ọ̀nà.+

Wọ́n dẹkùn fún mi.+ (Sélà)

6 Mo sọ fún Jèhófà pé: “Ìwọ ni Ọlọ́run mi.

Jèhófà, jọ̀wọ́ gbọ́ ẹ̀bẹ̀ mi fún ìrànlọ́wọ́.”+

7 Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ, Olùgbàlà mi tó lágbára,

O dáàbò bo orí mi ní ọjọ́ ogun.+

8 Jèhófà, má ṣe fún àwọn ẹni burúkú ní ohun tí ọkàn wọn fẹ́.

Má ṣe jẹ́ kí ohun tí wọ́n gbèrò bọ́ sí i, kí wọ́n má bàa gbé ara wọn ga.+ (Sélà)

9 Kí ọ̀rọ̀ ibi tí àwọn tó yí mi ká ń fẹnu wọn sọ+

Dà lé wọn lórí.

10 Kí òjò ẹyin iná rọ̀ lé wọn lórí.+

Ká jù wọ́n sínú iná,

Sínú àwọn kòtò jíjìn,*+ kí wọ́n má ṣe gbérí mọ́.

11 Kí àwọn abanijẹ́ má ṣe ríbi gbé nínú ayé.*+

Kí ibi máa lépa àwọn oníwà ipá, kó sì mú wọn balẹ̀.

12 Mo mọ̀ pé Jèhófà máa gbèjà àwọn aláìní

Á sì ṣèdájọ́ òdodo fún àwọn tálákà.+

13 Ó dájú pé àwọn olódodo yóò máa fi ọpẹ́ fún orúkọ rẹ;

Àwọn adúróṣinṣin yóò máa gbé níwájú* rẹ.+

Orin Dáfídì.

141 Jèhófà, mo ké pè ọ́.+

Tètè wá ràn mí lọ́wọ́.+

Fetí sílẹ̀ nígbà tí mo bá pè ọ́. +

2 Kí àdúrà mi dà bíi tùràrí+ tí a ṣètò sílẹ̀ níwájú rẹ,+

Kí ọwọ́ tí mo gbé sókè dà bí ọrẹ ọkà ìrọ̀lẹ́.+

3 Jèhófà, jọ̀wọ́ yan ẹ̀ṣọ́ fún ẹnu mi,

Kí o sì máa ṣọ́ ilẹ̀kùn ètè mi.+

4 Má ṣe jẹ́ kí ọkàn mi fà sí ohun búburú kankan,+

Kí n má bàa lọ́wọ́ sí iṣẹ́ ibi pẹ̀lú àwọn aṣebi;

Kí n má ṣe jẹ oúnjẹ aládùn wọn láé.

5 Tí olódodo bá gbá mi, á jẹ́ pé ó ní ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ sí mi;+

Tó bá bá mi wí, á dà bí òróró ní orí mi,+

Tí orí mi kò ní kọ̀ láé.+

Mi ò ní dákẹ́ àdúrà kódà nígbà tí àjálù bá bá wọn.

6 Bí a tilẹ̀ ju àwọn onídàájọ́ wọn sílẹ̀ láti ibi gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ àpáta,

Àwọn èèyàn yóò fetí sí ọ̀rọ̀ mi, torí pé ó lárinrin.

7 Bí ìgbà tí ẹnì kan bá ń tú ilẹ̀, tó sì ń tú u ká,

Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n tú egungun wa ká ní ẹnu Isà Òkú.*

8 Ojú rẹ ni mò ń wò, Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ.+

Ìwọ ni mo fi ṣe ibi ààbò mi.

Má ṣe gba ẹ̀mí mi.*

9 Dáàbò bò mí kí n má bàa kó sí ẹnu pańpẹ́ tí wọ́n dẹ dè mí,

Lọ́wọ́ ìdẹkùn àwọn aṣebi.

10 Àwọn ẹni burúkú lápapọ̀ yóò já sínú àwọ̀n tí àwọn fúnra wọn dẹ,+

Èmi á sì kọjá lọ láìséwu.

Másíkílì.* Ti Dáfídì, nígbà tó wà nínú ihò àpáta.+ Àdúrà.

142 Mo fi ohùn mi ké pe Jèhófà fún ìrànlọ́wọ́;+

Mo fi ohùn mi bẹ Jèhófà pé kó ṣojú rere sí mi.

2 Mo tú ẹ̀dùn ọkàn mi jáde níwájú rẹ̀;

Mo sọ nípa wàhálà mi níwájú rẹ̀+

3 Nígbà tí àárẹ̀ mú ẹ̀mí mi.*

Ò ń ṣọ́ ọ̀nà mi.+

Wọ́n dẹ pańpẹ́ pa mọ́ dè mí

Ní ọ̀nà tí mò ń rìn.

4 Wo ọwọ́ ọ̀tún mi, kí o sì rí i

Pé kò sẹ́ni tó rí tèmi rò.*+

Kò síbi tí mo lè sá lọ;+

Kò sẹ́ni tí ọ̀rọ̀ mi* ká lára.

5 Jèhófà, mo ké pè ọ́ fún ìrànlọ́wọ́.

Mo sọ pé: “Ìwọ ni ibi ààbò mi,+

Gbogbo ohun tí mo ní* lórí ilẹ̀ alààyè.”

6 Fetí sí igbe mi fún ìrànlọ́wọ́,

Nítorí wọ́n ti bá mi kanlẹ̀.

Gbà mí lọ́wọ́ àwọn tó ń ṣe inúnibíni sí mi,+

Torí wọ́n lágbára jù mí lọ.

7 Mú mi* jáde kúrò nínú àjà ilẹ̀

Kí n lè máa yin orúkọ rẹ.

Kí àwọn olódodo yí mi ká,

Nítorí o ti ṣemí lóore.

Orin Dáfídì.

143 Jèhófà, gbọ́ àdúrà mi;+

Gbọ́ ẹ̀bẹ̀ mi fún ìrànlọ́wọ́.

Dá mi lóhùn nínú òtítọ́ rẹ àti òdodo rẹ.

2 Má ṣe bá ìránṣẹ́ rẹ ṣẹjọ́,

Nítorí kò sí alààyè kankan tó lè jẹ́ olódodo níwájú rẹ.+

3 Nítorí ọ̀tá ń lépa mi;*

Ó ti tẹ ẹ̀mí mi mọ́lẹ̀.

Ó ti mú kí n máa gbé inú òkùnkùn bí àwọn tó ti kú tipẹ́tipẹ́.

4 Àárẹ̀ mú ẹ̀mí mi;*+

Ọkàn mi kú tipiri nínú mi.+

5 Mo rántí àwọn ọjọ́ àtijọ́;

Mo ṣe àṣàrò lórí gbogbo iṣẹ́ rẹ;+

Ó ń yá mi lára láti máa ronú lórí* iṣẹ́ ọwọ́ rẹ.

6 Mo tẹ́ ọwọ́ mi sí ọ;

Mò* ń wá ọ bí ilẹ̀ tó gbẹ táútáú ṣe ń wá òjò.+ (Sélà)

7 Jọ̀ọ́ Jèhófà, tètè dá mi lóhùn;+

Agbára* mi ti tán.+

Má fi ojú rẹ pa mọ́ fún mi,+

Kí n má bàa dà bí àwọn tó ń lọ sínú kòtò.*+

8 Ní àárọ̀, jẹ́ kí n gbọ́ nípa ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀,

Nítorí mo gbẹ́kẹ̀ lé ọ.

Jẹ́ kí n mọ ọ̀nà tó yẹ kí n máa rìn,+

Nítorí ìwọ ni mo yíjú sí.*

9 Gbà mí lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá mi, Jèhófà.

Ààbò rẹ ni mò ń wá.+

10 Kọ́ mi láti máa ṣe ìfẹ́ rẹ,+

Nítorí ìwọ ni Ọlọ́run mi.

Ẹ̀mí rẹ dára;

Kí ó máa darí mi ní ilẹ̀ tó tẹ́jú.*

11 Jèhófà, jọ̀wọ́ jẹ́ kí n máa wà láàyè nítorí orúkọ rẹ.

Gbà mí* nínú wàhálà nítorí òdodo rẹ.+

12 Pa àwọn ọ̀tá mi rẹ́*+ nítorí ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀;

Pa gbogbo àwọn tó ń halẹ̀ mọ́ mi* run,+

Nítorí ìránṣẹ́ rẹ ni mí.+

Ti Dáfídì.

144 Ìyìn ni fún Jèhófà, Àpáta mi,+

Ẹni tó ń kọ́ ọwọ́ mi ní ìjà

Àti ìka mi ní ogun.+

2 Òun ni ìfẹ́ mi tí kì í yẹ̀ àti ibi ààbò mi,

Ibi gíga mi tó láàbò àti olùgbàlà mi,

Apata mi àti Ẹni tí mo fi ṣe ibi ààbò,+

Ẹni tó ń tẹ àwọn èèyàn lórí ba sábẹ́ mi.+

3 Jèhófà, kí ni èèyàn jẹ́, tí o fi ń kíyè sí i

Àti ọmọ ẹni kíkú, tí o fi ń fiyè sí i?+

4 Èèyàn dà bí èémí lásán;+

Àwọn ọjọ́ rẹ̀ dà bí òjìji tó ń kọjá lọ.+

5 Jèhófà, tẹ àwọn ọ̀run rẹ wálẹ̀ kí o sì sọ̀ kalẹ̀;+

Fọwọ́ kan àwọn òkè, kí o sì mú kí wọ́n rú èéfín.+

6 Mú kí mànàmáná kọ, kí o sì tú àwọn ọ̀tá ká;+

Ta àwọn ọfà rẹ, kí o sì mú kí wọ́n wà nínú ìdàrúdàpọ̀.+

7 Na ọwọ́ rẹ jáde látòkè;

Dá mi sílẹ̀, kí o sì gbà mí lọ́wọ́ omi tó ń ru gùdù,

Lọ́wọ́* àwọn àjèjì,+

8 Àwọn tí ẹnu wọn ń parọ́,

Tí wọ́n sì ń gbé ọwọ́ ọ̀tún wọn sókè láti búra èké.*

9 Ọlọ́run, màá kọ orin tuntun sí ọ.+

Màá kọ orin ìyìn* sí ọ, pẹ̀lú ohun ìkọrin olókùn tín-ín-rín mẹ́wàá,

10 Sí Ẹni tó ń fún àwọn ọba ní ìṣẹ́gun,*+

Ẹni tó ń gba Dáfídì ìránṣẹ́ rẹ̀ sílẹ̀ lọ́wọ́ idà tó ń pani.+

11 Dá mi sílẹ̀, kí o sì gbà mí lọ́wọ́ àwọn àjèjì,

Àwọn tí ẹnu wọn ń parọ́,

Tí wọ́n sì ń gbé ọwọ́ ọ̀tún wọn sókè láti búra èké.

12 Nígbà náà, àwọn ọmọ wa yóò dà bí irúgbìn kékeré tó máa ń tètè dàgbà,

Àwọn ọmọbìnrin wa yóò dà bí àwọn òpó igun tí wọ́n ṣe fún ààfin.

13 Oríṣiríṣi irè oko yóò kún àwọn ilé ìkẹ́rùsí wa;

Àwọn agbo ẹran wa yóò di ìlọ́po ẹgbẹ̀rún, wọn yóò sì di ìlọ́po ẹgbẹẹgbàárùn-ún.

14 Àwọn ẹran ọ̀sìn wa tó lóyún kò ní fara pa,* oyún ò sì ní bà jẹ́ lára wọn;

Kò ní sí igbe wàhálà ní gbàgede ìlú wa.

15 Aláyọ̀ ni àwọn tó rí bẹ́ẹ̀ fún!

Aláyọ̀ ni àwọn tí Jèhófà jẹ́ Ọlọ́run wọn!+

Ìyìn Dáfídì.

א [Áléfì]

145 Màá gbé ọ ga, ìwọ Ọlọ́run mi Ọba,+

Màá yin orúkọ rẹ títí láé àti láéláé.+

ב [Bétì]

2 Màá yìn ọ́ láti àárọ̀ ṣúlẹ̀;+

Màá yin orúkọ rẹ títí láé àti láéláé.+

ג [Gímélì]

3 Jèhófà tóbi, òun sì ni ìyìn yẹ jù lọ,+

Àwámáridìí ni títóbi rẹ̀.*+

ד [Dálétì]

4 Ìran dé ìran yóò máa yin àwọn iṣẹ́ rẹ;

Wọ́n á máa sọ nípa iṣẹ́ ńlá rẹ.+

ה [Híì]

5 Wọ́n á máa sọ nípa ọlá ńlá ológo iyì rẹ,+

Màá sì máa ṣe àṣàrò lórí àwọn iṣẹ́ àgbàyanu rẹ.

ו [Wọ́ọ̀]

6 Wọ́n á máa sọ nípa àwọn iṣẹ́* àgbàyanu rẹ,

Màá sì máa kéde títóbi rẹ.

ז [Sáyìn]

7 Wọ́n á máa yọ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀ bí wọ́n ṣe ń sọ nípa ọ̀pọ̀ oore rẹ,+

Wọ́n á sì máa kígbe ayọ̀ nítorí òdodo rẹ.+

ח [Hétì]

8 Jèhófà jẹ́ agbatẹnirò* àti aláàánú,+

Kì í tètè bínú, ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ sì pọ̀ gidigidi.+

ט [Tétì]

9 Jèhófà ń ṣoore fún gbogbo ẹ̀dá,+

Àánú rẹ̀ sì wà lórí gbogbo iṣẹ́ rẹ̀.

י [Yódì]

10 Jèhófà, gbogbo iṣẹ́ rẹ yóò máa yìn ọ́ lógo,+

Àwọn ẹni ìdúróṣinṣin rẹ yóò sì máa yìn ọ́.+

כ [Káfì]

11 Wọ́n á máa kéde ògo ìjọba rẹ,+

Wọ́n á sì máa sọ̀rọ̀ nípa agbára rẹ,+

ל [Lámédì]

12 Kí aráyé lè mọ àwọn iṣẹ́ ńlá rẹ+

Àti ògo ọlá ńlá ìjọba rẹ.+

מ [Mémì]

13 Ìjọba ayérayé ni ìjọba rẹ,

Àkóso rẹ sì wà láti ìran dé ìran.+

ס [Sámékì]

14 Jèhófà ń gbé gbogbo àwọn tó ti fẹ́ ṣubú ró,+

Ó sì ń gbé gbogbo àwọn tó dorí kodò dìde.+

ע [Áyìn]

15 Ojú rẹ ni gbogbo ẹ̀dá ń wò,

Ò ń fún wọn ní oúnjẹ wọn lásìkò.+

פ [Péè]

16 O ṣí ọwọ́ rẹ,

O sì fún gbogbo ohun alààyè ní ohun tí wọ́n ń fẹ́.+

צ [Sádì]

17 Jèhófà jẹ́ olódodo ní gbogbo ọ̀nà rẹ̀,+

Ó sì jẹ́ adúróṣinṣin nínú gbogbo ohun tó ń ṣe.+

ק [Kófì]

18 Jèhófà wà nítòsí gbogbo àwọn tó ń ké pè é,+

Nítòsí gbogbo àwọn tó ń ké pè é ní òtítọ́.*+

ר [Réṣì]

19 Ó ń fún àwọn tó bẹ̀rù rẹ̀ ní ohun tí ọkàn wọn ń fẹ́;+

Ó ń gbọ́ igbe wọn fún ìrànlọ́wọ́, ó sì ń gbà wọ́n.+

ש [Ṣínì]

20 Jèhófà ń ṣọ́ gbogbo àwọn tó nífẹ̀ẹ́ rẹ̀,+

Àmọ́ yóò pa gbogbo ẹni burúkú run.+

ת [Tọ́ọ̀]

21 Ẹnu mi yóò kéde ìyìn Jèhófà;+

Kí gbogbo ohun alààyè* máa yin orúkọ mímọ́ rẹ̀ títí láé àti láéláé.+

146 Ẹ yin Jáà!*+

Kí gbogbo ara* mi yin Jèhófà.+

2 Màá yin Jèhófà ní gbogbo ọjọ́ ayé mi.

Màá kọ orin ìyìn* sí Ọlọ́run mi nígbà tí mo bá wà láàyè.

3 Ẹ má ṣe gbẹ́kẹ̀ lé àwọn olórí*

Tàbí lé ọmọ èèyàn, tí kò lè gbani là.+

4 Ẹ̀mí* rẹ̀ jáde lọ, ó pa dà sínú ilẹ̀;+

Ọjọ́ yẹn gan-an ni èrò inú rẹ̀ ṣègbé.+

5 Aláyọ̀ ni ẹni tí Ọlọ́run Jékọ́bù jẹ́ olùrànlọ́wọ́ rẹ̀,+

Tó gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà Ọlọ́run rẹ̀,+

6 Aṣẹ̀dá ọ̀run àti ayé,

Òkun àti gbogbo ohun tó wà nínú wọn,+

Ẹni tó jẹ́ olóòótọ́ nígbà gbogbo,+

7 Ẹni tó ń ṣe ìdájọ́ òdodo fún àwọn tí wọ́n lù ní jìbìtì,

Ẹni tó ń fún àwọn tí ebi ń pa lóúnjẹ.+

Jèhófà ń dá àwọn ẹlẹ́wọ̀n* sílẹ̀.+

8 Jèhófà ń la ojú àwọn afọ́jú;+

Jèhófà ń gbé àwọn tó sorí kọ́ dìde;+

Jèhófà nífẹ̀ẹ́ àwọn olódodo.

9 Jèhófà ń dáàbò bo àwọn àjèjì;

Ó ń fún ọmọ aláìníbaba àti opó lókun,+

Àmọ́, ó ń sọ èrò àwọn ẹni burúkú dòfo.*+

10 Jèhófà yóò jẹ Ọba títí láé,+

Àní Ọlọ́run rẹ, ìwọ Síónì, láti ìran dé ìran.

Ẹ yin Jáà!*

147 Ẹ yin Jáà!*

Ó dára láti máa kọ orin ìyìn* sí Ọlọ́run wa;

Ẹ wo bí ó ti dùn tó, tí ó sì tọ́ láti máa yìn ín!+

2 Jèhófà ń kọ́ Jerúsálẹ́mù;+

Ó ń kó àwọn tí wọ́n fọ́n ká lára Ísírẹ́lì jọ.+

3 Ó ń mú àwọn tó ní ọgbẹ́ ọkàn lára dá;

Ó ń di àwọn egbò wọn.

4 Ó ń ka iye àwọn ìràwọ̀;

Gbogbo wọn ni ó ń fi orúkọ pè.+

5 Olúwa wa tóbi, agbára rẹ̀ sì pọ̀;+

Òye rẹ̀ ò ṣeé díwọ̀n.+

6 Jèhófà ń gbé àwọn oníwà pẹ̀lẹ́ dìde,+

Àmọ́, ó ń rẹ àwọn ẹni burúkú wálẹ̀.

7 Ẹ kọrin sí Jèhófà pẹ̀lú ìdúpẹ́;

Ẹ fi háàpù kọ orin ìyìn sí Ọlọ́run wa,

8 Ẹni tó ń fi àwọsánmà bo ojú ọ̀run,

Ẹni tó ń pèsè òjò fún ayé,+

Ẹni tó ń mú kí koríko hù+ lórí àwọn òkè.

9 Ó ń fún àwọn ẹranko lóúnjẹ,+

Àwọn ọmọ ẹyẹ ìwò tó ń kígbe fún oúnjẹ.+

10 Kì í ṣe agbára ẹṣin ló ń mú inú rẹ̀ dùn;+

Bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe agbára ẹsẹ̀ èèyàn ló ń wú u lórí.+

11 Inú Jèhófà ń dùn sí àwọn tó bẹ̀rù rẹ̀,+

Sí àwọn tó ń dúró de ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀.+

12 Yin Jèhófà lógo, ìwọ Jerúsálẹ́mù.

Yin Ọlọ́run rẹ, ìwọ Síónì.

13 Ó ń mú kí ọ̀pá ìdábùú àwọn ẹnubodè rẹ lágbára;

Ó ń bù kún àwọn ọmọ rẹ nínú rẹ.

14 Ó ń mú àlàáfíà wá sórí ilẹ̀ rẹ;+

Ó ń fi àlìkámà* tó dára jù lọ* tẹ́ ọ lọ́rùn.+

15 Ó ń fi àṣẹ rẹ̀ ránṣẹ́ sí ayé;

Ọ̀rọ̀ rẹ̀ ń yára kánkán.

16 Ó ń fi yìnyín ránṣẹ́ bí ẹ̀gbọ̀n òwú;+

Ó ń fọ́n ìrì dídì ká bí eérú.+

17 Ó ń fi yìnyín* rẹ̀ sọ̀kò sílẹ̀ bí òkèlè.+

Ta ló lè fara da òtútù rẹ̀?+

18 Ó rán ọ̀rọ̀ rẹ̀ jáde, wọ́n sì yọ́.

Ó mú kí ẹ̀fúùfù rẹ̀ fẹ́,+ omi sì ń ṣàn.

19 Ó sọ ọ̀rọ̀ rẹ̀ fún Jékọ́bù,

Ó sọ àwọn ìlànà rẹ̀ àti àwọn ìdájọ́ rẹ̀ fún Ísírẹ́lì.+

20 Kò ṣe bẹ́ẹ̀ fún orílẹ̀-èdè míì;+

Wọn ò mọ nǹkan kan nípa ìdájọ́ rẹ̀.

Ẹ yin Jáà!*+

148 Ẹ yin Jáà!*

Ẹ yin Jèhófà láti ọ̀run;+

Ẹ yìn ín ní àwọn ibi gíga.

2 Ẹ yìn ín, gbogbo ẹ̀yin áńgẹ́lì rẹ̀.+

Ẹ yìn ín, gbogbo ẹ̀yin ọmọ ogun rẹ̀.+

3 Ẹ yìn ín, oòrùn àti òṣùpá.

Ẹ yìn ín, gbogbo ẹ̀yin ìràwọ̀ tó ń tàn.+

4 Ẹ yìn ín, ẹ̀yin ọ̀run gíga jù lọ*

Àti ẹ̀yin omi tó wà lókè àwọn ọ̀run.

5 Kí wọ́n máa yin orúkọ Jèhófà,

Nítorí ó pàṣẹ, a sì dá wọn.+

6 Ó fìdí wọn múlẹ̀ kí wọ́n lè wà títí láé àti láéláé;+

Ó pa àṣẹ tí kò ní kọjá lọ.+

7 Ẹ yin Jèhófà láti ayé,

Ẹ̀yin ẹ̀dá ńlá inú òkun àti gbogbo ẹ̀yin ibú omi,

8 Ẹ̀yin mànàmáná àti yìnyín ńlá, yìnyín kéékèèké àti ojú ọ̀run tó ṣú bolẹ̀,

Ìwọ ìjì líle, tó ń mú ọ̀rọ̀ rẹ̀ ṣẹ,+

9 Ẹ̀yin òkè ńlá àti gbogbo ẹ̀yin òkè kéékèèké,+

Ẹ̀yin igi eléso àti gbogbo ẹ̀yin igi kédárì,+

10 Ẹ̀yin ẹranko igbó+ àti gbogbo ẹ̀yin ẹran ọ̀sìn,

Ẹ̀yin ohun tó ń rákò àti ẹ̀yin ẹyẹ abìyẹ́,

11 Ẹ̀yin ọba ayé àti gbogbo ẹ̀yin orílẹ̀-èdè,

Ẹ̀yin olórí àti gbogbo ẹ̀yin onídàájọ́ ayé,+

12 Ẹ̀yin ọ̀dọ́kùnrin àti ẹ̀yin ọ̀dọ́bìnrin,*

Ẹ̀yin àgbà ọkùnrin àti ẹ̀yin ọ̀dọ́.*

13 Kí wọ́n máa yin orúkọ Jèhófà,

Nítorí orúkọ rẹ̀ nìkan ṣoṣo ló ga kọjá ibi tó ṣeé dé.+

Iyì rẹ̀ ga ju ayé àti ọ̀run lọ.+

14 Yóò gbé agbára* àwọn èèyàn rẹ̀ ga,

Ìyìn gbogbo àwọn ẹni ìdúróṣinṣin rẹ̀,

Ti àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, àwọn tó sún mọ́ ọn.

Ẹ yin Jáà!*

149 Ẹ yin Jáà!*

Ẹ kọ orin tuntun sí Jèhófà;+

Ẹ yìn ín nínú ìjọ àwọn adúróṣinṣin.+

2 Kí Ísírẹ́lì máa yọ̀ nínú Aṣẹ̀dá rẹ̀ Atóbilọ́lá;+

Kí inú àwọn ọmọ Síónì máa dùn nínú Ọba wọn.

3 Kí wọ́n máa fi ijó yin orúkọ rẹ̀+

Kí wọ́n sì máa kọ orin ìyìn* sí i, pẹ̀lú ìlù tanboríìnì àti háàpù.+

4 Nítorí inú Jèhófà ń dùn sí àwọn èèyàn rẹ̀.+

Ó ń fi ìgbàlà ṣe àwọn oníwà pẹ̀lẹ́ lọ́ṣọ̀ọ́.+

5 Kí àwọn adúróṣinṣin máa yọ̀ nínú ògo;

Kí wọ́n máa kígbe ayọ̀ lórí ibùsùn wọn.+

6 Kí orin ìyìn Ọlọ́run wà lẹ́nu wọn,

Kí idà olójú méjì sì wà lọ́wọ́ wọn,

7 Láti gbẹ̀san lára àwọn orílẹ̀-èdè,

Kí wọ́n sì fìyà jẹ àwọn èèyàn,

8 Láti fi ẹ̀wọ̀n de àwọn ọba wọn,

Kí wọ́n sì fi ṣẹkẹ́ṣẹkẹ̀ de àwọn èèyàn pàtàkì wọn,

9 Láti mú ìdájọ́ tó ti wà lákọsílẹ̀ nípa wọn ṣẹ.+

Iyì yìí jẹ́ ti gbogbo àwọn adúróṣinṣin rẹ̀.

Ẹ yin Jáà!*

150 Ẹ yin Jáà!*+

Ẹ yin Ọlọ́run nínú ibi mímọ́ rẹ̀.+

Ẹ yìn ín nínú òfúrufú* agbára rẹ̀.+

2 Ẹ yìn ín nítorí àwọn iṣẹ́ ńlá rẹ̀.+

Ẹ yìn ín nítorí títóbi rẹ̀ tó ta yọ.+

3 Ẹ fun ìwo láti fi yìn ín.+

Ẹ fi ohun ìkọrin olókùn tín-ín-rín àti háàpù yìn ín.+

4 Ẹ fi ìlù tanboríìnì+ àti ijó àjóyípo yìn ín.

Ẹ fi àwọn nǹkan olókùn tín-ín-rín+ àti fèrè*+ yìn ín.

5 Ẹ fi àwọn síńbálì* tó ń dún yìn ín.

Ẹ fi àwọn síńbálì+ tó ń dún gooro yìn ín.

6 Kí gbogbo ohun tó ń mí yin Jáà.

Ẹ yin Jáà!*+

Tàbí “ṣe àṣàrò lórí.”

Ìyẹn, èèpo fúlẹ́fúlẹ́ ara ọkà.

Tàbí “ṣe àṣàrò lórí ohun asán.”

Tàbí “gbìmọ̀ pọ̀.”

Tàbí “Kristi.”

Tàbí “Ẹ ṣọ́ra.”

Ní Héb., “Ẹ fẹnu ko ọmọ náà lẹ́nu.”

Ní Héb., “ó.”

Tàbí “ọkàn mi.”

Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.

Ní Héb., “àyè fífẹ̀.”

Tàbí “mú kí ẹni ìdúróṣinṣin rẹ̀ yàtọ̀; ya ẹni ìdúróṣinṣin rẹ̀ sọ́tọ̀ fún ara rẹ̀.”

Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.

Tàbí “ẹni tó ń ta ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀ tó sì ń tanni jẹ.”

Tàbí “ibi mímọ́.”

Tàbí “Wọ́n ń lo ahọ́n dídùn.”

Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.

Tàbí “Ṣàánú mi.”

Tàbí “ọkàn mi.”

Tàbí “ọkàn mi.”

Tàbí “rántí.”

Tàbí “Ṣìọ́ọ̀lù,” ìyẹn ibojì aráyé. Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.

Ní Héb., “ń mú kí ibùsùn mi lúwẹ̀ẹ́.”

Tàbí “gbó.”

Tàbí “ọ̀fọ̀.”

Tàbí “ọkàn mi.”

Tàbí kó jẹ́, “Tí mo sì dá ẹni tó ń ta kò mí sí láìnídìí.”

Tàbí “ọkàn mi.”

Tàbí “dán ọkàn àti kíndìnrín wò.”

Tàbí “rọ̀jò ìdálẹ́bi.”

Tàbí “Ọlẹ̀.”

Tàbí “kọ orin sí.”

Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.

Tàbí kó jẹ́, “Ìwọ tí à ń ròyìn iyì rẹ lókè ọ̀run.”

Tàbí “àwọn áńgẹ́lì.”

Ní Héb., “àwọn ẹranko inú pápá.”

Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.

Tàbí “kọ orin sí.”

Tàbí “ilẹ̀ tó ń méso jáde.”

Tàbí “ibi gíga tó láàbò.”

Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.

Tàbí “Ṣìọ́ọ̀lù,” ìyẹn ibojì aráyé. Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.

Tàbí kó jẹ́, “Olójúkòkòrò ń súre fún ara rẹ̀.”

Tàbí “Ó ń wú fùkẹ̀ sí gbogbo àwọn ọ̀tá rẹ̀.”

Tàbí “Mi ò ní ta gọ̀ọ́gọ̀ọ́ (gbọ̀n-ọ́n gbọ̀n-ọ́n).”

Tàbí “nínú igbó.”

Tàbí “àwọn èékánná rẹ̀ tó lágbára.”

Tàbí “aláìlóbìí.”

Ní Héb., “tó jẹ́ ará ayé.”

Tàbí “ọkàn mi.”

Tàbí “ọṣán.”

Tàbí “ìpìlẹ̀ ìdájọ́ òdodo.”

Tàbí “tó ń tàn yanran.”

Tàbí “Ọkàn rẹ̀; Òun alára.”

Tàbí kó jẹ́, “rọ̀jò ẹyin iná sórí.”

Tàbí “ojú rere.”

Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.

Ní Héb., “Wọ́n ń fi ètè dídùn sọ̀rọ̀.”

Ní Héb., “ọkàn àti ọkàn.”

Tàbí “tó ń fi wọ́n ṣẹ̀sín.”

Tàbí kó jẹ́, “ìléru tí wọ́n fi ń yọ́ irin, tí wọ́n ṣe sórí ilẹ̀.”

Tàbí “ọkàn mi.”

Tàbí “hùwà sí mi lọ́nà tó ń mérè wá.”

Tàbí “Òpònú.”

Tàbí “pẹ̀lú ìwà títọ́.”

Tàbí “dójú ti àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀.”

Ní Héb., “ìbúra.”

Tàbí “kò ní ta gọ̀ọ́gọ̀ọ́ (gbọ̀n-ọ́n gbọ̀n-ọ́n) láé.”

Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.

Ìyẹn, orúkọ àwọn ọlọ́run èké.

Tàbí “inú mi lọ́hùn-ún.” Ní Héb., “kíndìnrín mi.”

Tàbí “mi ò ní ta gọ̀ọ́gọ̀ọ́ (gbọ̀n-ọ́n gbọ̀n-ọ́n).”

Ní Héb., “ògo.”

Tàbí “Ara mi.”

Tàbí “o ò ní pa ọkàn mi tì.”

Tàbí “Ṣìọ́ọ̀lù,” ìyẹn ibojì aráyé. Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.

Tàbí kó jẹ́, “ìdíbàjẹ́.”

Ní Héb., “ojú.”

Tàbí “Adùn.”

Tàbí “Bẹ̀rẹ̀ kí o sì fetí sí mi.”

Tàbí “àwọn ọ̀tá tó ń wá ọkàn mi.”

Tàbí “Ọ̀rá wọn ti bò wọ́n lára.”

Tàbí “tì wá ṣubú.”

Tàbí “ọkàn mi.”

Tàbí “ètò àwọn nǹkan.”

Tàbí “láti rí ìrísí rẹ.”

Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.

Tàbí “olùgbàlà mi tó lágbára.”

Tàbí “ibi gíga mi tó láàbò.”

Tàbí “Ṣìọ́ọ̀lù,” ìyẹn ibojì aráyé. Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.

Tàbí “ìyẹ́ afẹ́fẹ́.”

Tàbí “Ipa odò.”

Tàbí “ibi tó láyè fífẹ̀.”

Tàbí “mo jẹ́ aláìmọwọ́mẹsẹ̀.”

Tàbí “àwọn tí ìyà ń jẹ.”

Ní Héb., “àwọn olójú gíga.”

Tàbí “akónilẹ́rù.”

Tàbí “ń gbé mi ró.”

Tàbí “ọrùn ẹsẹ̀.”

Tàbí “Wàá jẹ́ kí n gbá ẹ̀yìn ọrùn àwọn ọ̀tá mi mú.”

Ní Héb., “lẹ́nu mọ́.”

Tàbí “Àwọn àjèjì á pòórá.”

Tàbí “kọ orin sí.”

Tàbí “ìṣẹ́gun.”

Ní Héb., “èso.”

Tàbí “Òfúrufú.”

Tàbí kó jẹ́, “okùn ìdíwọ̀n wọn ti.”

Tàbí “ilẹ̀ tó ń mú èso jáde.”

Tàbí “mú ọkàn sọ jí (pa dà wá).”

Tàbí “tí a yọ́ mọ́.”

Tàbí “ọ̀pọ̀ ìrélànàkọjá.”

Ní Héb., “ka ẹbọ sísun rẹ sí èyí tó lọ́ràá.”

Tàbí “ìmọ̀ràn.”

Tàbí “ìṣẹ́gun.”

Tàbí “tí a yọ́ mọ́.”

Ní Héb., “Ọjọ́ gígùn.”

Ní Héb., “ojú rẹ.”

Tàbí “kò ní ta gọ̀ọ́gọ̀ọ́ (gbọ̀n-ọ́n gbọ̀n-ọ́n).”

Ní Héb., “èso.”

Ní Héb., “okùn ọrun.”

Ní Héb., “ojú wọn.”

Ní Héb., “kọrin, a ó sì lo ohun ìkọrin fún.”

Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ ohùn orin tàbí oríṣi orin kan.

Tàbí “O gúnwà láàárín (lórí) ìyìn Ísírẹ́lì.”

Tàbí “dójú tì wọ́n.”

Tàbí “Ẹni ẹ̀gàn ni mí lójú àwọn èèyàn.”

Ní Héb., “ni wọ́n jù mí sí.”

Tàbí “Gba ọkàn mi.”

Ní Héb., “ọ̀kan ṣoṣo mi,” ó ń tọ́ka sí ọkàn tàbí ẹ̀mí rẹ̀.

Ní Héb., “ọwọ́.”

Ní Héb., “èso.”

Ní Héb., “èso.”

Ní Héb., “Kí ọkàn yín wà.”

Ní Héb., “àwọn tó sanra.”

Tàbí “ọkàn.”

Ní Héb., “Èso kan.”

Tàbí kó jẹ́, “síbi omi tó pa rọ́rọ́.”

Tàbí “Ó tu ọkàn mi.”

Ìyẹn, ọ̀pá tí orí rẹ̀ rí rubutu.

Tàbí “ń tù mí nínú.”

Tàbí “tu orí mi lára.”

Tàbí “ọkàn Mi,” ó ń tọ́ka sí wíwàláàyè Jèhófà tí àwọn èèyàn fi ń búra.

Tàbí “ìdájọ́ òdodo.”

Tàbí “Ẹ nàró.”

Tàbí “gbé ọkàn mi.”

Tàbí “Èyí tó ti wà láti ayébáyé.”

Ní Héb., “nínú ìdájọ́.”

Tàbí “Ọkàn rẹ̀ yóò.”

Ní Héb., “Èso.”

Tàbí “ọkàn.”

Ní Héb., “ra Ísírẹ́lì pa dà.”

Tàbí “inú mi lọ́hùn-ún.” Ní Héb.,“kíndìnrín mi.”

Ní Héb., “jókòó.”

Tàbí “Èmi kì í bá àwọn alágàbàgebè ṣe wọléwọ̀de.”

Ní Héb., “jókòó.”

Tàbí “ọkàn mi.”

Tàbí “àwọn tó ń ta ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀.”

Ní Héb., “Rà mí pa dà.”

Ní Héb., “àwọn àpéjọ.”

Tàbí “àròjinlẹ̀.”

Tàbí “ibi mímọ́.”

Tàbí “kọrin sí.”

Tàbí “Má ṣe jẹ́ kí ìfẹ́ àwọn elénìní mi ṣẹ lé mi lórí.”

Tàbí kó jẹ́, “Mo gbà gbọ́ dájú pé màá rí oore Jèhófà ní ilẹ̀ alààyè.”

Tàbí “sàréè.”

Tàbí “jọ́sìn.”

Tàbí kó jẹ́, “nítorí ògo ìjẹ́mímọ́ rẹ̀.”

Ó ṣe kedere pé, agbègbè olókè Lẹ́bánónì ló ń sọ.

Tàbí “òkun tó wà ní ọ̀run.”

Tàbí “fà mí.”

Tàbí “ọkàn mi.”

Tàbí “Ṣìọ́ọ̀lù,” ìyẹn ibojì aráyé. Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.

Tàbí “sàréè.”

Tàbí “kọrin sí.”

Ní Héb., “ìrántí.”

Tàbí “inú rere.”

Tàbí “Mi ò ní ta gọ̀ọ́gọ̀ọ́ (gbọ̀n-ọ́n gbọ̀n-ọ́n).”

Tàbí “fi inú rere hàn sí mi.”

Ní Héb., “ẹ̀jẹ̀.”

Tàbí “sàréè.”

Ní Héb., “aṣọ àpò ìdọ̀họ.”

Tàbí “ògo mi.”

Tàbí “Bẹ̀rẹ̀ kí o sì fetí sí mi.”

Tàbí “Ọlọ́run olóòótọ́.”

Tàbí “ìdààmú ọkàn mi.”

Tàbí “ibi tó láyè fífẹ̀.”

Tàbí “ọkàn mi àti ikùn mi.”

Tàbí “Wọn ò fiyè sí mi mọ́.”

Tàbí “ọkàn.”

Ní Héb., “àwọn àkókò.”

Tàbí “Ṣìọ́ọ̀lù,” ìyẹn ibojì aráyé. Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.

Ní Héb., “lọ́wọ́ ìjà ahọ́n.”

Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.

Tàbí “dárí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ jì.”

Tàbí “ìbínú.”

Tàbí “Ọ̀rinrin ayé mi ti yí pa dà.”

Ọ̀rọ̀ yìí ní Hébérù ń tọ́ka sí ìbaaka.

Tàbí “Ẹ kọ orin sí i.”

Tàbí “ẹ̀mí.”

Ní Héb., “àwọn ọmọ ogun wọn.”

Tàbí “ìmọ̀ràn àwọn orílẹ̀-èdè.”

Tàbí “èrò.”

Tàbí “ìmọ̀ràn.”

Tàbí “fúnni ní ìṣẹ́gun.”

Tàbí “ọkàn wọn.”

Tàbí “Ọkàn wa.”

Tàbí “Ọkàn mi.”

Tàbí “ọmọ kìnnìún tó tó ọdẹ ṣe (onígọ̀gọ̀).”

Tàbí “tí ìrẹ̀wẹ̀sì bá.”

Tàbí “Àjálù.”

Tàbí “ọkàn.”

Apata kékeré tí àwọn tafàtafà sábà máa ń gbé dání.

Tàbí “àáké olórí méjì.”

Tàbí “ọkàn mi.”

Tàbí “ọkàn mi.”

Ìyẹn, èèpo fúlẹ́fúlẹ́ ara ọkà.

Tàbí “ọkàn mi.”

Tàbí “ọkàn mi.”

Tàbí “ọkàn mi.”

Ní Héb., “aṣọ àpò ìdọ̀họ.”

Tàbí “ọkàn mi.”

Tàbí “bá pa dà sí àyà mi.”

Tàbí kó jẹ́, “Àwọn tí kò ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run ń fini ṣẹ̀sín nítorí búrẹ́dì.”

Tàbí “ọkàn mi.”

Ní Héb., “ọ̀kan ṣoṣo mi,” ó ń tọ́ka sí ọkàn rẹ̀ tàbí ẹ̀mí rẹ̀.

Tàbí “ọmọ kìnnìún tó tó ọdẹ ṣe (onígọ̀gọ̀).”

Tàbí “Àháà! Ọkàn wa.”

Tàbí “ṣàṣàrò lórí.”

Ní Héb., “dà bí àwọn òkè Ọlọ́run.”

Tàbí “gbà là.”

Ní Héb., “mu ọ̀rá.”

Tàbí “gbaná jẹ.”

Tàbí “ilẹ̀ náà.”

Tàbí “Ní ayọ̀ tó kọyọyọ.”

Ní Héb., “Yí ọ̀nà rẹ sọ́dọ̀ Jèhófà.”

Tàbí “fi sùúrù dúró.”

Tàbí kó jẹ́, “Má ṣe bínú, torí á mú kí o ṣe ibi.”

Tàbí “fi okùn sí.”

Ní Héb., “àwọn ọjọ́ àwọn aláìlẹ́bi.”

Tàbí “ń ṣàánú.”

Tàbí “mú kí ẹsẹ̀ ẹni múlẹ̀.”

Tàbí “fi ọwọ́ Rẹ̀ dì í mú.”

Ní Héb., “búrẹ́dì.”

Tàbí “ń fi ohùn jẹ́ẹ́jẹ́ẹ́ sọ ọ̀rọ̀ ọgbọ́n.”

Tàbí “ẹni tó ń pa ìwà títọ́ mọ́.”

Tàbí “láti ránni létí.”

Ní Héb., “Kò sí ibì kankan tó dá ṣáṣá lára mi.”

Ní Héb., “Iná gba abẹ́ mi kan.”

Tàbí “ké ramúramù.”

Ní Héb., “Ìmọ́lẹ̀ ojú mi sì ti lọ.”

Tàbí “ọkàn.”

Ní Héb., “wà láàyè.”

Tàbí kó jẹ́, “Àwọn tó sọ ara wọn di ọ̀tá mi láìnídìí pọ̀.”

Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.

Tàbí “ru sókè.”

Ní Héb., “ti gbóná.”

Tàbí “ń kẹ́dùn.”

Tàbí “bí ọjọ́ ayé mi ṣe kéré tó.”

Ní Héb., “jẹ́ ìbú ọwọ́.”

Ní Héb., “ń pariwo.”

Tàbí “kòkòrò.”

Tàbí “Olùtẹ̀dó.”

Tàbí “Mo fi sùúrù.”

Tàbí “Ó tẹ̀ ba láti gbọ́ mi.”

Tàbí “onírọ́.”

Tàbí “kọ́ ló ń múnú rẹ dùn.”

Tàbí “ni ó wù mí.”

Tàbí “ọkàn mi.”

Tàbí “ìfẹ́ ọkàn.” Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.

Tàbí “ọkàn mi.”

Tàbí “yíjú pa dà sí mi.”

Tàbí “Láti ayérayé dé ayérayé.”

Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.

Tàbí “Ọkàn mi.”

Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.

Tàbí “máa ń rọra rìn.”

Tàbí “ọkàn.”

Tàbí “ọkàn.”

Tàbí “òkè kékeré.”

Tàbí kó jẹ́, “bíi pé wọ́n ń fọ́ egungun mi.”

Tàbí “ọkàn.”

Tàbí “ọkàn.”

Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.

Tàbí “Fún Jékọ́bù ní ìgbàlà ńlá.”

Ní Héb., “ọrun.”

Tàbí “látinú iye owó wọn.”

Ní Héb., “àfipòwe.”

Tàbí “akátá.”

Tàbí “ọkàn wa.”

Ní Héb., “Rà wá pa dà.”

Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.

Ní Héb., “Àwọn iṣẹ́ mi jẹ́ nípa.”

Tàbí “gègé.”

Tàbí “akọ̀wé òfin.”

Tàbí “ṣàṣeyọrí.”

Ní Héb., “kọ́ ọ ní.”

Tàbí “ìdájọ́ òdodo.”

Tàbí “Olorì.”

Tàbí “tù ọ́ lójú.”

Ní Héb., “Nínú.”

Ní Héb., “A lẹ àwọn ohun ọ̀ṣọ́ wúrà mọ́ aṣọ rẹ̀.”

Tàbí kó jẹ́, “aṣọ tí a kóṣẹ́ sí lára.”

Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.

Tàbí “yọ ìfófòó.”

Tàbí “ibi gíga wa tó láàbò.”

Tàbí kó jẹ́, “àwọn apata.”

Tàbí “ìwo àgbò; kàkàkí.”

Tàbí “Ẹ kọrin.”

Ní Héb., “àwọn apata.”

Tàbí “ibi gíga tó láàbò.”

Tàbí “pàdé bí wọ́n ṣe ṣàdéhùn.”

Ní Héb., “ọmọbìnrin.”

Tàbí “odi ààbò.”

Tàbí kó jẹ́, “títí a ó fi kú.”

Tàbí “inú ètò àwọn nǹkan.”

Ní Héb., “Ẹ̀yin ọmọ ìran èèyàn àti ẹ̀yin ọmọ èèyàn.”

Ní Héb., “àṣìṣe.”

Tàbí “ọkàn.”

Tàbí “sàréè.”

Tàbí “Ṣìọ́ọ̀lù,” ìyẹn ibojì aráyé. Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.

Tàbí “Ṣìọ́ọ̀lù,” ìyẹn ibojì aráyé. Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.

Tàbí “ọkàn mi.”

Ní Héb., “kúrò ní ọwọ́.”

Tàbí “Ṣìọ́ọ̀lù,” ìyẹn ibojì aráyé. Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.

Tàbí “ọkàn.”

Tàbí “Olú Ọ̀run, Ọlọ́run, Jèhófà.”

Tàbí “Láti ìlà oòrùn dé ìwọ̀ oòrùn.”

Ní Héb., “òbúkọ.”

Ìyẹn, akọ màlúù.

Tàbí “ẹ̀kọ́.”

Ní Héb., “ń ju ọ̀rọ̀ mi sí ẹ̀yìn rẹ.”

Tàbí kó jẹ́, “o dara pọ̀ mọ́ ọn.”

Tàbí “sọ̀rọ̀ ọmọ ìyá rẹ láìdáa.”

Tàbí “lọ́kàn mi.”

Ní Héb., “Ìwọ nìkan.”

Tàbí “Ẹlẹ́ṣẹ̀ sì ni mí látìgbà tí ìyá mi ti.”

Tàbí “ọkàn mi.”

Tàbí “Pa ojú rẹ mọ́.”

Tàbí “nu gbogbo ìṣìnà mi kúrò.”

Ní Héb., “Kí o sì fún mi ní ẹ̀mí ìmúratán.”

Tàbí “fojú pa ọkàn tó gbọgbẹ́ tó sì ní ìdààmú rẹ́.”

Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.

Tàbí “odi ààbò.”

Ní Héb., “Àgbákò látọwọ́ rẹ̀.”

Tàbí “fi ṣe ibi ààbò.”

Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.

Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.

Tàbí “Òpònú.”

Tàbí kó jẹ́, “Ẹ̀rù á bà wọ́n níbi tí kò sí ohun tó ń bani lẹ́rù.”

Ní Héb., “tó dó tì ọ́.”

Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.

Tàbí “gba ẹjọ́ mi rò.”

Tàbí “ọkàn.”

Tàbí “Wọn kì í ro ti Ọlọ́run.”

Tàbí “ti ọkàn mi.”

Ní Héb., “Pa wọ́n lẹ́nu mọ́.”

Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.

Tàbí “Má sì fara pa mọ́ nígbà tí mo bá bẹ̀ ọ́ fún ìrànlọ́wọ́.”

Ní Héb., “pín ahọ́n wọn níyà.”

Tàbí “èèyàn, tí a jọ jẹ́ ẹgbẹ́.”

Tàbí “Ṣìọ́ọ̀lù,” ìyẹn ibojì aráyé. Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.

Tàbí “kígbe.”

Ní Héb., “rà mí pa dà.”

Tàbí “ọkàn mi.”

Ìyẹn, ọ̀rẹ́ àtijọ́ tí ẹsẹ 13 àti 14 sọ.

Tàbí “ta gọ̀ọ́gọ̀ọ́; ta gbọ̀n-ọ́n gbọ̀n-ọ́n.”

Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.

Tàbí “ń kù gìrì mọ́ mi.”

Ní Héb., “ẹran ara.”

Tàbí “ọkàn mi.”

Tàbí “ọkàn mi.”

Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.

Tàbí “ọkàn mi.”

Tàbí “ọkàn mi.”

Tàbí “ọkàn mi.”

Tàbí “kọ orin sí ọ.”

Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.

Tàbí “ya oníwà ìbàjẹ́.”

Ní Héb., “látinú ilé ọmọ wá.”

Tàbí “ọmọ kìnnìún tó tó ọdẹ ṣe (onígọ̀gọ̀).”

Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.

Ní Héb., “ilé náà.”

Tàbí “àwọn tí òùngbẹ ẹ̀jẹ̀ ń gbẹ.”

Tàbí “de ọkàn mi.”

Tàbí “gbó.”

Tàbí “ru.”

Tàbí “ibi gíga mi tó láàbò.”

Tàbí “gbó.”

Tàbí “kọrin sí.”

Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.

Tàbí kó jẹ́, “O ti fún.”

Ní Héb., “ọrun.”

Tàbí kó jẹ́, “ibi mímọ́.”

Tàbí “Pẹ̀tẹ́lẹ̀.”

Irú èyí tí àwọn ọmọ ogun máa ń dé. Ní Héb., “odi agbára.”

Tàbí kó jẹ́, “ìlú olódi.”

Tàbí “àárẹ̀ mú.”

Tàbí “Màá jẹ́ àlejò.”

Ní Héb., “fi kún ọjọ́ ayé ọba.”

Tàbí “máa gbé.”

Tàbí “Yan ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ àti òtítọ́ fún un.”

Tàbí “kọ orin sí.”

Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.

Tàbí “ọkàn mi.”

Tàbí “ibi gíga mi tó láàbò.”

Tàbí kó jẹ́, “Gbogbo yín, bíi pé ó jẹ́ ògiri tó dagun, ògiri olókùúta tó ti fẹ́ wó.”

Tàbí “ipò iyì rẹ̀.”

Tàbí “ìwọ ọkàn mi.”

Tàbí “Òùngbẹ rẹ ń gbẹ mí.”

Ní Héb., “ara mi.”

Tàbí “ọkàn mi.”

Ní Héb., “Bí ẹni tó jẹ ọ̀rá, tó sì sanra ni a ṣe tẹ́ mi lọ́rùn.”

Tàbí “Ọkàn mi.”

Tàbí “ọkàn mi; pa mí.”

Tàbí “kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀.”

Tàbí “ṣògo.”

Tàbí “Wọ́n fún ara wọn ní ìṣírí láti ṣe ibi.”

Tàbí “yangàn.”

Ní Héb., “gbogbo ẹlẹ́ran ara.”

Tàbí “ibi mímọ́.”

Ní Héb., “Ó.”

Ní Héb., “Ó.”

Ní Héb., “Ó.”

Ní Héb., “kí ó kún àkúnwọ́sílẹ̀.”

Ní Héb., “ọkà.”

Ìyẹn, àárín ebè.

Tàbí “ebè rẹ̀ tí a kọ.”

Ní Héb., “Ọ̀rá ń kán tótó ní ojú ọ̀nà rẹ.”

Ní Héb., “ń kán tótó.”

Tàbí “pẹ̀tẹ́lẹ̀.”

Tàbí “kọrin sí.”

Tàbí “Ó pa ọkàn wa mọ́ láàyè.”

Tàbí “ta gọ̀ọ́gọ̀ọ́; ta gbọ̀n-ọ́n gbọ̀n-ọ́n.”

Ní Héb., “lé ìbàdí wa.”

Ní Héb., “gun orí wa.”

Tàbí “ọkàn mi.”

Tàbí “bọlá fún un.”

Tàbí “kọrin sí.”

Tàbí kó jẹ́, “tó ń gun àwọsánmà.”

“Jáà” ni ìkékúrú Jèhófà.

Ní Héb., “onídàájọ́.”

Tàbí “àwọn ọlọ̀tẹ̀.”

Ní Héb., “lọ níwájú.”

Ní Héb., “kán tótó.”

Ní Héb., “ogún.”

Tàbí kó jẹ́, “ọgbà àgùntàn.”

Tàbí “tó ní àwọ̀ yẹ́lò àti ti ewé.”

Tàbí “Ṣe ló dà bíi pé yìnyín bọ́ ní Sálímónì.”

Tàbí “òkè ọlọ́lá.”

Tàbí “fẹ́.”

Tàbí “tó ń rìn.”

Ní Héb., “àwọn àpéjọ.”

Ìyẹn, koríko etí omi.

Tàbí kó jẹ́, “tẹ fàdákà mọ́lẹ̀.”

Tàbí kó jẹ́, “Àwọn ikọ̀ yóò.”

Tàbí “kọrin sí.”

Ní Héb., “àwọsánmà.”

Ní Héb., “rẹ.”

Tàbí “ọkàn mi ti fẹ́ bómi lọ.”

Tàbí “Àwọn tó di ọ̀tá mi láìnídìí.”

Tàbí “ọkàn.”

Tàbí kó jẹ́, “Nígbà tí mo sunkún tí mo sì gbààwẹ̀.”

Ní Héb., “aṣọ àpò ìdọ̀họ.”

Ní Héb., “àfipòwe.”

Tàbí “kòtò.”

Tàbí “Sún mọ́ ọkàn mi, kí o sì gbà á pa dà.”

Tàbí “ó le débi pé ìrẹ̀wẹ̀sì bá mi.”

Tàbí “Ewéko onímájèlé.”

Ní Héb., “ìbàdí.”

Tàbí “ìrunú.”

Tàbí “ibùdó wọn tó ní ògiri yí ká.”

Tàbí “ìwé ìyè.”

Ìyẹn, ilẹ̀ náà.

Tàbí “láti múni rántí.”

Tàbí “ọkàn.”

Tàbí “Bẹ̀rẹ̀ kí o sì fetí sí mi.”

Tàbí “ìgbọ́kànlé mi.”

Tàbí “ọkàn.”

Tàbí “ta ko ọkàn mi.”

Tàbí “kà.”

Ní Héb., “apá.”

Tàbí “ibú omi.”

Tàbí “fi háàpù kọrin sí ọ.”

Tàbí “o ti ra ọkàn mi pa dà.”

Tàbí “ṣe àṣàrò lórí.”

Ní Héb., “dá ẹjọ́.”

Ní Héb., “rú jáde.”

Tàbí “ṣàkóso.”

Ìyẹn, odò Yúfírétì.

Tàbí “owó òde.”

Tàbí “ọkàn.”

Tàbí “ra ọkàn wọn pa dà.”

Tàbí “ọkà.”

Tàbí “àwọn tó ń fọ́nnu.”

Tàbí “Ikùn wọn tóbi bẹ̀ǹbẹ̀.”

Ní Héb., “Ọ̀rá.”

Ìyẹn, àwọn èèyàn Ọlọ́run.

Ní Héb., “ìran àwọn ọmọ.”

Ní Héb., “fojú àbùkù wò wọ́n.”

Ní Héb., “Kíndìnrín mi.”

Tàbí “lọ hùwà àìṣòótọ́.”

Ní Héb., “pa lẹ́nu mọ́.”

Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.

Ní Héb., “rú èéfín.”

Ní Héb., “àpéjọ rẹ.”

Tàbí “àpéjọ.”

Tàbí “Gbogbo ibi tí wọ́n ti ń sin Ọlọ́run.”

Tàbí “láti ibi tó ṣẹ́ po lára aṣọ rẹ.”

Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.

Tàbí “orísun ìmọ́lẹ̀.”

Tàbí “ọkàn.”

Ní Héb., “ìwo.”

Ní Héb., “ìwo.”

Tàbí “kọrin sí.”

Ní Héb., “ìwo.”

Ní Héb., “ìwo.”

Tàbí “Ìmọ́lẹ̀ bò ọ́ pátápátá.”

Ní Héb., “ẹ̀mí.”

Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.

Ní Héb., “ọwọ́ mi ò kú tipiri.”

Tàbí “ọkàn mi.”

Ní Héb., “ẹ̀mí mi dá kú.”

Tàbí “orin tí mo fi ohun ìkọrin olókùn tín-ín-rín kọ.”

Ní Héb., “Ẹ̀mí mi.”

Tàbí “tó ń gún.”

Ní Héb., “yí ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ pa dà.”

Ní Héb., “apá.”

Ní Héb., “ra àwọn èèyàn rẹ pa dà.”

Tàbí “ilẹ̀ tó ń méso jáde.”

Ní Héb., “Nípa ọwọ́.”

Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.

Tàbí “ìtọ́ni.”

Ní Héb., “tí ọkàn wọn ò múra sílẹ̀.”

Ní Héb., “ọrun.”

Tàbí “ògiri.”

Tàbí “àwọsánmà.”

Ní Héb., “dán Ọlọ́run wò.”

Tàbí “oúnjẹ fún ọkàn wọn.”

Tàbí “àwọn áńgẹ́lì.”

Tàbí “Olùgbẹ̀san.”

Ní Héb., “Ó máa ń bo ẹ̀ṣẹ̀ wọn.”

Tàbí kó jẹ́, “Pé ẹ̀mí ń jáde lọ, kì í sì í pa dà wá.”

Tàbí “Wọ́n sì ṣe ohun tó dun.”

Ní Héb., “ọwọ́.”

Ní Héb., “rà wọ́n pa dà.”

Tàbí kó jẹ́, “fi ibà amáragbóná fòfò.”

Tàbí “ọkàn wọn.”

Ní Héb., “ẹ̀mí wọn.”

Ní Héb., “dán Ọlọ́run Ẹni Gíga Jù Lọ wò.”

Tàbí “mú kí ó jowú.”

Ní Héb., “A kò sì yin.”

Ní Héb., “Ó kọ́ ibi mímọ́ rẹ̀ kí ó ga bí òkè.”

Ní Héb., “bo àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa mọ́lẹ̀.”

Ní Héb., “apá.”

Tàbí kó jẹ́, “dá . . . sílẹ̀.”

Ní Héb., “àwọn ọmọ ikú.”

Tàbí kó jẹ́, “láàárín.”

Tàbí “Fi ìmọ́lẹ̀ rẹ hàn.”

Ní Héb., “runú.”

Ìyẹn, odò Yúfírétì.

Tàbí “ìmàdò.”

Tàbí “Igi àjàrà.”

Tàbí “ẹ̀ka.”

Ní Héb., “Nígbà tí ojú rẹ bá wọn wí.”

Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.

Tàbí “èdè.”

Ní Héb., “láti ibi tí ààrá fara pa mọ́ sí.”

Ó túmọ̀ sí “Ìjà.”

Ní Héb., “Wọ́n rìn nínú ìmọ̀ràn ara wọn.”

Ní Héb., “Ìgbà wọn.”

Tàbí “wíìtì.”

Ní Héb., “ọ̀rá àlìkámà.”

Ní Héb., “ọ,” ìyẹn, àwọn èèyàn Ọlọ́run.

Tàbí “àpéjọ Olú Ọ̀run.”

Tàbí “àwọn ẹni bí Ọlọ́run.”

Tàbí “dá ẹjọ́.”

Tàbí “ẹni bí Ọlọ́run.”

Tàbí “Má pa ẹnu mọ́.”

Tàbí “ń gbé orí wọn sókè.”

Ní Héb., “àwọn tí o fi pa mọ́.”

Ní Héb., “Wọ́n jọ gbàmọ̀ràn pẹ̀lú ọkàn kan.”

Tàbí “dá májẹ̀mú.”

Ní Héb., “Wọ́n ti di apá fún àwọn ọmọ Lọ́ọ̀tì.”

Tàbí “àfonífojì.”

Tàbí “àwọn aṣáájú.”

Tàbí “ewéko gbígbẹ tí atẹ́gùn ń gbé kiri.”

Ní Héb., “kún ojú wọn.”

Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.

Tàbí “Mo mà fẹ́ràn àgọ́ ìjọsìn rẹ títóbi lọ́lá o.”

Tàbí “Ọkàn mi ń ṣàárò.”

Tàbí “àfonífojì àwọn igi bákà.”

Tàbí kó jẹ́, “Olùkọ́ sì fi ìbùkún bo ara rẹ̀ bí aṣọ.”

Tàbí kó jẹ́, “Ìwọ Ọlọ́run, wo apata wa.”

Ní Héb., “O bo gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ wọn.”

Tàbí “Kó wa pa dà.”

Tàbí “aásìkí.”

Tàbí “Bẹ̀rẹ̀ kí o sì fetí sí mi.”

Tàbí “ọkàn.”

Tàbí “ọkàn ìránṣẹ́ rẹ.”

Tàbí “gbé ọkàn mi.”

Tàbí “Mú ọkàn mi ṣọ̀kan.”

Tàbí “ọkàn.”

Tàbí “Ṣìọ́ọ̀lù,” ìyẹn ibojì aráyé. Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.

Tàbí “ọkàn.”

Tàbí “Wọn ò fi tìrẹ pè.”

Tàbí “olóore ọ̀fẹ́.”

Tàbí “òtítọ́.”

Tàbí “ẹ̀rí.”

Tàbí “bọlá fún mi.”

Tàbí “Ní tèmi, ìwọ ni orísun ohun gbogbo.”

Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.

Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.

Tàbí “Bẹ̀rẹ̀ kí o sì fetí sí.”

Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.

Tàbí “Ṣìọ́ọ̀lù,” ìyẹn ibojì aráyé. Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.

Tàbí “sàréè.”

Tàbí “Mo dà bí ọkùnrin tí kò lágbára.”

Ní Héb., “ọwọ́.”

Tàbí “ti sọ di aláìlágbára.”

Tàbí “ní Ábádónì.”

Tàbí “ọkàn mi.”

Tàbí kó jẹ́, “lẹ́ẹ̀kan náà.”

Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.

Tàbí “wà.”

Ní Héb., “èso.”

Tàbí “àpéjọ.”

Ní Héb., “ìwo.”

Tàbí “owó òde.”

Ní Héb., “ìwo.”

Ní Héb., “àṣẹ.”

Ní Héb., “èso.”

Tàbí “àwọn ìdájọ́.”

Tàbí “ọ̀tẹ̀.”

Ní Héb., “Mi ò sì ní parọ́ ní ti òtítọ́ mi.”

Ní Héb., “èso.”

Tàbí “dáyádémà.”

Tàbí “àwọn àgọ́.”

Ní Héb., “O ti gbé ọwọ́ ọ̀tún àwọn elénìní rẹ̀ sókè.”

Tàbí “ọkàn.”

Ní Héb., “ní ọwọ́ Ṣìọ́ọ̀lù,” ìyẹn, ibojì aráyé. Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.

Ní Héb., “gbé ẹ̀gàn gbogbo èèyàn lé àyà mi.”

Tàbí kó jẹ́, “ibi ààbò.”

Tàbí “kí o tó bí ayé àti ilẹ̀ tó ń méso jáde nínú ìrora ìbímọ.”

Tàbí “Láti ayé àìnípẹ̀kun títí dé ayé àìnípẹ̀kun.”

Tàbí “O mọ àwọn àṣìṣe wa.”

Tàbí “Ẹ̀mí wa.”

Tàbí “èémí àmíkanlẹ̀.”

Tàbí “nítorí agbára tó ṣàrà ọ̀tọ̀.”

Tàbí “fìdí múlẹ̀.”

Tàbí “fìdí múlẹ̀.”

Tàbí “bo ọ̀nà àbáwọlé rẹ.”

Tàbí “ògiri.”

Ní Héb., “ẹ̀san.”

Tàbí kó jẹ́, “ibi ààbò; odi ààbò.”

Tàbí “kìnnìún tó tó ọdẹ ṣe.”

Ní Héb., “ó ti dara pọ̀ mọ́ mi.”

Tàbí “bọlá fún.”

Tàbí “rí ìgbàlà láti ọ̀dọ̀ mi.”

Tàbí “kọrin sí.”

Tàbí “èpò.”

Ní Héb., “wàá gbé ìwo mi ga.”

Tàbí “nígbà orí ewú.”

Ní Héb., “Wọ́n á sanra.”

Tàbí “Ilẹ̀ tó ń méso jáde.”

Tàbí “Kò lè ta gbọ̀n-ọ́n gbọ̀n-ọ́n.”

Tàbí “ìjẹ́mímọ́ yẹ.”

Ní Héb., “gbin.”

Tàbí “ọkàn mi ì bá.”

Ní Héb., “ti máa gbé inú ìdákẹ́jẹ́ẹ́.”

Tàbí “ìrònú tó ń gbéni lọ́kàn sókè.”

Tàbí “pọ̀ nínú mi.”

Tàbí “Ìtùnú rẹ tu ọkàn mi lára.”

Tàbí “àwọn alákòóso tó ní; àwọn onídàájọ́ tó ní.”

Tàbí “fi àṣẹ.”

Tàbí “sí ọkàn olódodo.”

Ní Héb., “Wọ́n dá ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ lẹ́bi (pe ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ ní burúkú).”

Tàbí “ibi gíga tó láàbò.”

Ní Héb., “lẹ́nu mọ́.”

Ní Héb., “lẹ́nu mọ́.”

Tàbí “ọ̀dọ̀.”

Ní Héb., “ọwọ́ rẹ̀.”

Ó túmọ̀ sí “Ìjà.”

Ó túmọ̀ sí “Àdánwò.”

Tàbí “iyì.”

Tàbí “jọ́sìn.”

Tàbí kó jẹ́, “nítorí ògo ìjẹ́mímọ́ rẹ̀.”

Tàbí “Ilẹ̀ tó ń méso jáde.”

Tàbí “kò lè ta gbọ̀n-ọ́n gbọ̀n-ọ́n.”

Tàbí “gba ẹjọ́ àwọn èèyàn rò.”

Tàbí “ó ti dé.”

Tàbí “ilẹ̀ tó ń méso jáde.”

Tàbí “jọ́sìn rẹ̀.”

Ní Héb., “àwọn ọmọbìnrin.”

Tàbí “ọkàn.”

Tàbí “kúrò ní ìkáwọ́.”

Ní Héb., “ìrántí.”

Tàbí “ti jẹ́ kó ṣẹ́gun.”

Tàbí “ìṣẹ́gun.”

Tàbí “kọrin.”

Tàbí “kọrin.”

Tàbí “Ilẹ̀ tó ń méso jáde.”

Tàbí “ó ti dé láti.”

Tàbí “ilẹ̀ tó ń méso jáde.”

Tàbí kó jẹ́,“láàárín.”

Tàbí “jọ́sìn.”

Tàbí “àwọsánmà tó rí bí òpó.”

Ní Héb., “o gbẹ̀san lára wọn.”

Tàbí “jọ́sìn.”

Tàbí “gbà.”

Tàbí kó jẹ́, “kì í ṣe àwa fúnra wa.”

Tàbí “kọrin sí.”

Tàbí “ìwà títọ́.”

Tàbí “ohun tí kò wúlò.”

Tàbí “Ìwà wọn kò mọ́ mi lára.”

Ní Héb., “mọ.”

Tàbí “mú un kúrò.”

Tàbí “nínú ìwà títọ́.”

Tàbí “lọ́dọ̀.”

Tàbí “mú gbogbo àwọn ẹni burúkú ayé kúrò.”

Tàbí “tí àárẹ̀ mú un.”

Tàbí “Bẹ̀rẹ̀ kí o sì fetí sí mi.”

Tàbí kó jẹ́, “Mo ti rù kan eegun.”

Tàbí “tó ń dá yẹ̀yẹ́ mi sílẹ̀.”

Tàbí “òjìji àṣálẹ́.”

Tàbí “Orúkọ rẹ yóò sì wà.” Ní Héb., “Ìrántí.”

Ní Héb., “dá.”

Ní Héb., “Má ṣe mú mi kúrò ní ààbọ̀ àwọn ọjọ́ mi.”

Tàbí “ọkàn mi.”

Tàbí “ọkàn mi.”

Tàbí “sàréè.”

Ní Héb., “ìgbà ọ̀dọ́.”

Tàbí “jẹ́ olóore ọ̀fẹ́.”

Tàbí “inú-rere-onífẹ̀ẹ́ rẹ̀.”

Ní Héb., “Àyè rẹ̀ kò sì mọ̀ ọ́n mọ́.”

Tàbí “láti ayérayé dé ayérayé.”

Ní Héb., “tí ẹ sì ń gbọ́ ohùn (ìró) ọ̀rọ̀ rẹ̀.”

Tàbí “ibi tó wà lábẹ́ àṣẹ rẹ̀.”

Tàbí “ọkàn.”

Tàbí “ọkàn mi.”

Tàbí “iyì.”

Ní Héb., “sínú omi.”

Tàbí “mú kí ó ta gbọ̀n-ọ́n gbọ̀n-ọ́n.”

Tàbí “Èso iṣẹ́.”

Tàbí “ọmọ kìnnìún tó tó ọdẹ ṣe (onígọ̀gọ̀).”

Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.

Tàbí “kọrin.”

Tàbí kó jẹ́, “Kí ohun tí mò ń rò nípa rẹ̀ dùn mọ́ni.”

Tàbí “ọkàn mi.”

Tàbí “Halelúyà!” “Jáà” ni ìkékúrú Jèhófà.

Tàbí “kọ orin fún un.”

Tàbí kó jẹ́, “sọ nípa.”

Tàbí “ibi tó wà.”

Tàbí “àtọmọdọ́mọ.” Ní Héb., “èso.”

Ní Héb., “ọ̀rọ̀ tó pa láṣẹ.”

Ní Héb., “Ó ṣẹ́ gbogbo ọ̀pá búrẹ́dì.” Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ àwọn ọ̀pá tí wọ́n fi ń tọ́jú búrẹ́dì pa mọ́.

Ní Héb., “jẹ ẹsẹ̀ rẹ̀ níyà.”

Tàbí “Ọkàn rẹ̀ wọnú irin.”

Ní Héb., “Kó lè de.”

Tàbí “bó bá ṣe tẹ́ ọkàn rẹ̀ lọ́rùn.”

Tàbí “ọwọ́ iná.”

Ní Héb., “wọn.”

Tàbí “ìkùukùu.”

Tàbí “Halelúyà!” “Jáà” ni ìkékúrú Jèhófà.

Tàbí “Halelúyà!” “Jáà” ni ìkékúrú Jèhófà.

Tàbí “ṣoore fún.”

Tàbí “máa fi ọ́ yangàn.”

Tàbí “lóye ìtúmọ̀.”

Tàbí “aginjù.”

Tàbí “tó ṣẹ́ kù.”

Tàbí “ọkàn wọn.”

Tàbí “ère dídà.”

Ní Héb., “dúró sí àlàfo níwájú rẹ̀.”

Tàbí “so ara wọn mọ́.”

Ìyẹn, ẹbọ tí wọ́n rú sí òkú èèyàn tàbí sí àwọn ọlọ́run tí kò lẹ́mìí.

Ó túmọ̀ sí “Ìjà.”

Tàbí “Wọ́n sì kọ́ ìṣe wọn.”

Ní Héb., “Wọ́n sì wà lábẹ́ ọwọ́ wọn.”

Tàbí “Á kẹ́dùn.”

Tàbí “ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ tó pọ̀ gidigidi.”

Tàbí “yọ̀ nínú ìyìn rẹ.”

Tàbí “Láti ayérayé dé ayérayé.”

Tàbí “Kó rí bẹ́ẹ̀!”

Tàbí “Halelúyà!” “Jáà” ni ìkékúrú Jèhófà.

Tàbí “rà.”

Tàbí “gbà kúrò ní ìkáwọ́.”

Tàbí “Láti yíyọ oòrùn àti láti wíwọ̀ oòrùn.”

Tàbí “ọkàn wọn.”

Tàbí “ọkàn.”

Tàbí “Ọkàn wọn kọ gbogbo oúnjẹ.”

Ní Héb., “ní ìjókòó.”

Ìyẹn, koríko etí omi.

Tàbí “ó gbé àwọn aláìní ga,” ìyẹn, kí ọwọ́ má bàa tó wọn.

Ní Héb., “Kódà màá fi ògo mi.”

Tàbí “kọ orin sí ọ.”

Tàbí kó jẹ́, “ibi mímọ́.”

Tàbí “Pẹ̀tẹ́lẹ̀.”

Irú èyí tí àwọn ọmọ ogun máa ń dé. Ní Héb., “odi agbára.”

Tàbí “afinisùn.”

Tàbí “kí wọ́n pè é ní ẹni burúkú.”

Ní Héb., “àwọn ọmọkùnrin.”

Ní Héb., “àwọn ọmọkùnrin.”

Tàbí “ẹni tó ń gba èlé gọbọi dẹ pańpẹ́ mú.”

Tàbí “ìfẹ́ tí kì í yẹ̀.”

Tàbí “ìran àtẹ̀lé.”

Tàbí “fi ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ hàn.”

Tàbí “ọkàn mi.”

Ní Héb., “Ara mi ti rù, láìní ọ̀rá (òróró).”

Tàbí “aṣọ àwọ̀lékè tí kò lápá.”

Tàbí “ọkàn rẹ̀.”

Tàbí “ní ọjọ́ tí àwọn ọmọ ogun rẹ kóra jọ.”

Ní Héb., “láti ilé ọlẹ̀ ọ̀yẹ̀.”

Tàbí “yí ìpinnu rẹ̀ pa dà.”

Tàbí “láàárín.”

Ní Héb., “olórí.”

Tàbí “gbogbo ayé.”

Ó ń tọ́ka sí “Olúwa mi” inú ẹsẹ 1.

Tàbí “Halelúyà!” “Jáà” ni ìkékúrú Jèhófà.

Tàbí “olóore ọ̀fẹ́.”

Ní Héb., “pa wọ́n.”

Tàbí “Halelúyà!” “Jáà” ni ìkékúrú Jèhófà.

Tàbí “olóore ọ̀fẹ́.”

Tàbí “pẹ̀lú oore ọ̀fẹ́.”

Tàbí “kò ṣe ségesège.”

Tàbí “fàlàlà.”

Ní Héb., “ìwo.”

Tàbí “Halelúyà!” “Jáà” ni ìkékúrú Jèhófà.

Tàbí “tó gúnwà sí.”

Tàbí kó jẹ́, “ààtàn.”

Ní Héb., “àwọn ọmọkùnrin.”

Tàbí “Halelúyà!” “Jáà” ni ìkékúrú Jèhófà.

Ìyẹn, koríko etí omi.

Tàbí “Kò sóhun tó jẹ́ tiwa, Jèhófà, kò sóhun tó jẹ́ tiwa.”

Ní Héb., “àwọn ọmọkùnrin.”

Ní Héb., “sínú ìdákẹ́jẹ́ẹ́.”

Tàbí “Halelúyà!” “Jáà” ni ìkékúrú Jèhófà.

Tàbí kó jẹ́, “Mo nífẹ̀ẹ́ nítorí Jèhófà ń gbọ́.”

Tàbí “ó ń bẹ̀rẹ̀ kí ó lè fetí.”

Ní Héb., “ní ọjọ́ ayé mi.”

Ní Héb., “Àwọn ìdààmú Ṣìọ́ọ̀lù wá mi rí.”

Tàbí “gba ọkàn mi.”

Tàbí “olóore ọ̀fẹ́.”

Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.

Tàbí “gba ọkàn mi.”

Tàbí “ìgbàlà ńlá.”

Ní Héb., “iyebíye.”

Tàbí “Halelúyà!” “Jáà” ni ìkékúrú Jèhófà.

Tàbí “agbo ilé.”

Tàbí “Halelúyà!” “Jáà” ni ìkékúrú Jèhófà.

“Jáà” ni ìkékúrú Jèhófà.

Tàbí “ibi tó láyè fífẹ̀.”

Tàbí kó jẹ́, “pẹ̀lú àwọn tó ń ràn mí lọ́wọ́.”

Tàbí kó jẹ́, “O.”

Tàbí “ìṣẹ́gun.”

Ní Héb., “olórí igun.”

Tàbí “àwọn tó ń pa ìwà títọ́ mọ́.”

Ní Héb., “Ì bá ṣe pé àwọn ọ̀nà mi fìdí múlẹ̀ gbọn-in.”

Tàbí “kẹ́kọ̀ọ́ nípa.”

Ní Héb., “Yí ẹ̀gàn àti àbùkù kúrò lórí mi.”

Tàbí “kẹ́kọ̀ọ́ nípa rẹ̀.”

Tàbí “Ọkàn mi.”

Ní Héb., “ọ̀nà.”

Tàbí “kẹ́kọ̀ọ́ nípa.”

Tàbí “ọkàn mi.”

Tàbí “kí ojú tì mí.”

Ní Héb., “Màá sáré ní.”

Tàbí kó jẹ́, “o mú kí ọkàn mi ní ìgboyà.”

Tàbí “Mú mi rìn.”

Tàbí “Kó má ṣe fà sí èrè.”

Tàbí “ọ̀rọ̀ tí o sọ.”

Tàbí kó jẹ́, “Èyí tí o ṣe fún àwọn tó bẹ̀rù rẹ.”

Tàbí “sọ.”

Tàbí “mo dúró de.”

Tàbí “ibi tó láyè fífẹ̀.”

Tàbí “kẹ́kọ̀ọ́ nípa.”

Tàbí “ìlérí tí o ṣe.”

Tàbí “Èyí tí o mú kí n dúró dè.”

Tàbí “Ní ilé tí mo ti jẹ́ àjèjì.”

Tàbí “tù ọ́ lójú (wá ẹ̀rín rẹ).”

Tàbí “sọ.”

Tàbí “mo máa ń dẹ́ṣẹ̀ láì mọ̀ọ́mọ̀.”

Ní Héb., “kú tipiri, bí ọ̀rá.”

Tàbí “ni mo dúró dè.”

Tàbí “ọ̀rọ̀ tí o sọ.”

Tàbí kó jẹ́, “wọ́n ń parọ́ mọ́ mi.”

Tàbí “kẹ́kọ̀ọ́ nípa.”

Tàbí “Ọkàn mi ń kú lọ nítorí.”

Tàbí “ni mo dúró dè.”

Ìyẹn, gbogbo ohun tó dá.

Ní Héb., “gbòòrò gan-an.”

Tàbí “kẹ́kọ̀ọ́ nípa rẹ̀.”

Tàbí “kẹ́kọ̀ọ́ nípa.”

Ní Héb., “ọrẹ àtọkànwá ẹnu mi.”

Tàbí “Ọkàn mi wà ní ọwọ́ mi.”

Tàbí “ogún mi ayérayé.”

Ní Héb., “tẹ ọkàn mi.”

Tàbí “àwọn tí ọkàn wọn pínyà.”

Tàbí “Màá dúró de ọ̀rọ̀ rẹ.”

Tàbí “sọ.”

Tàbí “ìtìjú.”

Ní Héb., “ìdàrọ́.”

Ní Héb., “ẹran ara.”

Tàbí “ọ̀rọ̀.”

Tàbí “tí a yọ́ mọ́.”

Tàbí “àṣẹ.”

Tàbí “ọkàn mi.”

Ní Héb., “mí hẹlẹ.”

Tàbí “mú kí ìṣísẹ̀ mi ṣe tààrà.”

Ní Héb., “Rà mí pa dà.”

Tàbí “rẹ́rìn-ín sí.”

Tàbí “nígbà tí ọ̀yẹ̀ ń là.”

Tàbí “ni mò ń dúró dè.”

Tàbí “kẹ́kọ̀ọ́ nípa.”

Tàbí “ìwà tó ń ríni lára.”

Tàbí “Gba ẹjọ́ mi rò.”

Tàbí “sọ.”

Tàbí “Kò sí ohun ìkọ̀sẹ̀ kankan fún wọn.”

Tàbí “Ọkàn mi.”

Tàbí “sọ.”

Ní Héb., “Kí ìyìn máa dà ní ètè mi.”

Tàbí “ọkàn mi.”

Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.

Tàbí “gba ọkàn mi.”

Ní Héb., “kí ni Òun yóò sì fi kún un fún ọ?”

Tàbí “Ọkàn mi.”

Tàbí “ta gbọ̀n-ọ́n gbọ̀n-ọ́n.”

Tàbí “ọkàn.”

Ní Héb., “ṣọ́ ìjáde àti ìwọlé rẹ.”

“Jáà” ni ìkékúrú Jèhófà.

Tàbí “àwọn odi ààbò rẹ.”

Tàbí “fi ọkàn wa ṣẹ̀sín kọjá bó ṣe yẹ.”

Tàbí “ọkàn wa.”

Tàbí “bo ọkàn wa.”

Tàbí “Ọkàn wa.”

Tàbí “rawọ́ lé.”

Tàbí “mú.”

Tàbí “Bí àwọn àfonífojì tó wà ní gúúsù.”

Ní Héb., “ọmọkùnrin.”

Tàbí “ilé ọlẹ̀.”

Ìyẹn, àárín ebè.

“Jáà” ni ìkékúrú Jèhófà.

Tàbí “ṣọ́.”

Ní Héb., “bẹ̀rù rẹ.”

Tàbí “ọkàn.”

Tàbí “Ọkàn mi.”

Tàbí “ọkàn mi.”

Tàbí “ara.”

Tàbí “Ọkàn mi.”

Tàbí “Àgọ́ ìjọsìn títóbi.”

Tàbí “àgọ́ ìjọsìn rẹ̀ títóbi.”

Ní Héb., “yí ojú ẹni àmì òróró rẹ pa dà.”

Ní Héb., “èso ilé ọmọ.”

Ní Héb., “kí ìwo Dáfídì yọ.”

Tàbí “dáyádémà.”

Tàbí kó jẹ́, “ní ibi mímọ́.”

Tàbí “Halelúyà!” “Jáà” ni ìkékúrú Jèhófà.

Tàbí “kọrin.”

Tàbí “ohun ìní rẹ̀ tó ṣeyebíye.”

Tàbí “oruku.”

Tàbí kó jẹ́, “ọ̀ṣọ̀ọ̀rọ̀.”

Tàbí “orúkọ rẹ yóò wà.” Ní Héb., “ìrántí.”

Tàbí “gba ẹjọ́ àwọn èèyàn rẹ̀ rò.”

Tàbí “kẹ́dùn nítorí.”

Tàbí “òye.”

Ní Héb., “sí ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀.”

Ní Héb., “gbogbo ẹlẹ́ran ara.”

Ó ń tọ́ka sí Bábílónì.

Tàbí kó jẹ́, “Kí ọwọ́ ọ̀tún mi rọ.”

Tàbí kó jẹ́, “Láìfi ti àwọn ọlọ́run mìíràn pè, màá kọrin sí ọ.”

Tàbí “ibi mímọ́ rẹ.”

Tàbí kó jẹ́, “o ti gbé ọ̀rọ̀ rẹ ga ju orúkọ ìwọ fúnra rẹ lọ.”

Tàbí “ọkàn mi.”

Ní Héb., “díwọ̀n.”

Tàbí “yà mí lẹ́nu gan-an.”

Tàbí “jinlẹ̀ ju ohun tí mo lè lóye.”

Tàbí “Ṣìọ́ọ̀lù,” ìyẹn ibojì aráyé. Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.

Tàbí kó jẹ́, “hun mí.”

Tàbí “Ọkàn mi.”

Tàbí “tí mo ṣì jẹ́ ọlẹ̀.”

Tàbí kó jẹ́., “màá ṣì máa kà wọ́n.”

Tàbí “ẹlẹ́bi ẹ̀jẹ̀.”

Tàbí “lórí èrò tiwọn.”

Tàbí “tó ń dà mí lọ́kàn rú.”

Tàbí “kòtò olómi.”

Tàbí “lórí ilẹ̀.”

Tàbí “lọ́dọ̀.”

Tàbí “Ṣìọ́ọ̀lù,” ìyẹn ibojì aráyé. Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.

Tàbí “tú ọkàn mi jáde.”

Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.

Tàbí “tí mi ò lágbára mọ́.”

Ní Héb., “tó dá mi mọ̀.”

Tàbí “ọ̀rọ̀ ọkàn mi.”

Ní Héb., “Ìpín mi.”

Tàbí “ọkàn mi.”

Tàbí “ọkàn mi.”

Tàbí “Mi ò lágbára mọ́.”

Tàbí “kẹ́kọ̀ọ́ nípa.”

Tàbí “Ọkàn mi.”

Ní Héb., “Ẹ̀mí.”

Tàbí “sàréè.”

Tàbí “ìwọ ni mo gbé ọkàn mi sókè sí.”

Tàbí “ilẹ̀ adúróṣinṣin.”

Tàbí “Gba ọkàn mi.”

Ní Héb., “lẹ́nu mọ́.”

Tàbí “ọkàn mi.”

Tàbí “Ní ìkáwọ́.”

Ní Héb., “Tí ọwọ́ ọ̀tún wọn sì jẹ́ ọwọ́ ọ̀tún ẹ̀tàn.”

Tàbí “kọrin.”

Tàbí “ìgbàlà.”

Tàbí “bẹ́ níkùn.”

Tàbí “Títóbi rẹ̀ kọjá òye ẹ̀dá.”

Tàbí “nípa agbára.”

Tàbí “olóore ọ̀fẹ́.”

Tàbí “tó ń fòótọ́ inú ké pè é.”

Ní Héb., “gbogbo ẹran ara.”

Tàbí “Halelúyà!” “Jáà” ni ìkékúrú Jèhófà.

Tàbí “ọkàn.”

Tàbí “kọrin.”

Tàbí “èèyàn pàtàkì.”

Tàbí “Èémí.”

Ní Héb., “àwọn tí a dè.”

Tàbí “sọ ọ̀nà àwọn ẹni burúkú di wíwọ́.”

Tàbí “Halelúyà!” “Jáà” ni ìkékúrú Jèhófà.

Tàbí “Halelúyà!” “Jáà” ni ìkékúrú Jèhófà.

Tàbí “kọrin.”

Tàbí “wíìtì.”

Ní Héb., “ọ̀rá àlìkámà.”

Tàbí “omi dídì.”

Tàbí “Halelúyà!” “Jáà” ni ìkékúrú Jèhófà.

Tàbí “Halelúyà!” “Jáà” ni ìkékúrú Jèhófà.

Ní Héb., “ọ̀run àwọn ọ̀run.”

Ní Héb., “wúńdíá.”

Tàbí “arúgbó àti ọ̀dọ́.”

Ní Héb., “ìwo.”

Tàbí “Halelúyà!” “Jáà” ni ìkékúrú Jèhófà.

Tàbí “Halelúyà!” “Jáà” ni ìkékúrú Jèhófà.

Tàbí “kọrin.”

Tàbí “Halelúyà!” “Jáà” ni ìkékúrú Jèhófà.

Tàbí “Halelúyà!” “Jáà” ni ìkékúrú Jèhófà.

Tàbí “ojú ọ̀run tó ń jẹ́rìí sí.”

Tàbí “ape.”

Tàbí “aro.”

Tàbí “Halelúyà!” “Jáà” ni ìkékúrú Jèhófà.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́